The Old Testament of the Holy Bible

Genesisi 1

Ìtàn bí a ṣe dá ayé

1 Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. 2 Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. 3 Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. 4 Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. 5 Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini. 6 Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi. 7 Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃. 8 Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji. 9 Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃. 10 Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara. 11 Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. 12 Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 13 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta. 14 Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún: 15 Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃. 16 Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu. 17 Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ, 18 Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara. 19 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin. 20 Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun. 21 Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 22 Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ. 23 Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun. 24 Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃. 25 Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 26 Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 27 Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn. 28 Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 29 Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio ma ṣe onjẹ fun. 30 Ati fun gbogbo ẹranko ilẹ, ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrakò lori ilẹ, ti iṣe alaye, ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ: o si ri bẹ̃. 31 Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹfa.

Genesisi 2

1 BẸ li a pari ọrun on aiye, ati gbogbo ogun wọn. 2 Ni ijọ́ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ́ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. 3 Ọlọrun si busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹ̀rẹ si iṣe. 4 Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ́ ti OLUWA Ọlọrun dá aiye on ọrun.

Ọgbà Edẹni

5 Ati olukuluku igi igbẹ ki o to wà ni ilẹ, ati olukuluku eweko igbẹ ki nwọn ki o to hù: OLUWA Ọlọrun kò sa ti rọ̀jo si ilẹ, kò si sí enia kan lati ro ilẹ. 6 Ṣugbọn ikũku a ti ilẹ wá, a si ma rin oju ilẹ gbogbo. 7 OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn. 8 OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si. 9 Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu. 10 Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin. 11 Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà; 12 Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki. 13 Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká. 14 Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate. 15 OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ. 16 OLUWA Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki o ma jẹ: 17 Ṣugbọn ninu igi ìmọ rere ati bururu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kikú ni iwọ o kú. 18 OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. 19 Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀. 20 Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. 21 OLUWA Ọlọrun si mu orun ìjika kùn Adamu, o si sùn: o si yọ ọkan ninu egungun-ìha rẹ̀, o si fi ẹran di ipò rẹ̀: 22 OLUWA Ọlọrun si fi egungun-ìha ti o mu ni ìha ọkunrin na mọ obinrin, o si mu u tọ̀ ọkunrin na wá. 23 Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a o ma pè e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá. 24 Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan. 25 Awọn mejeji si wà ni ìhoho, ati ọkunrin na ati obinrin rẹ̀, nwọn kò si tiju.

Genesisi 3

Ìwà Àìgbọràn

1 EJÒ sa ṣe alarekereke jù ẹranko igbẹ iyoku lọ ti OLUWA Ọlọrun ti dá. O si wi fun obinrin na pe, õtọ li Ọlọrun wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ gbogbo eso igi ọgbà? 2 Obinrin na si wi fun ejò na pe, Awa a ma jẹ ninu eso igi ọgbà: 3 Ṣugbọn ninu eso igi nì ti o wà lãrin ọgbà Ọlọrun ti wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn a, ki ẹnyin ki o má ba kú. 4 Ejò na si wi fun obinrin na pe, Ẹnyin ki yio ku ikú kikú kan. 5 Nitori Ọlọrun mọ̀ pe, li ọjọ́ ti ẹnyin ba jẹ ninu rẹ̀, nigbana li oju nyin yio là, ẹnyin o si dabi Ọlọrun, ẹ o mọ̀ rere ati buburu. 6 Nigbati obinrin na si ri pe, igi na dara ni jijẹ, ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a ifẹ lati mu ni gbọ́n, o mu ninu eso rẹ̀ o si jẹ, o si fi fun ọkọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, on si jẹ. 7 Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn. 8 Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà. 9 OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà? 10 O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́. 11 O si wi pe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wà ni ìhoho? iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ kò gbọdọ jẹ? 12 Ọkunrin na si wipe, Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ. 13 OLUWA Ọlọrun si bi obinrin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obinrin na si wipe, Ejò li o tàn mi, mo si jẹ.

Ọlọrun Ṣèdájọ́

14 OLUWA Ọlọrun si wi fun ejò na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o ma fi wọ́, erupẹ ilẹ ni iwọ o ma jẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo. 15 Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ. 16 Fun obinrin na li o wipe, Emi o sọ ipọnju ati iloyun rẹ di pupọ̀; ni ipọnju ni iwọ o ma bimọ; lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yio ma fà si, on ni yio si ma ṣe olori rẹ. 17 O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gbà ohùn aya rẹ gbọ́, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; 18 Ẹgún on oṣuṣu ni yio ma hù jade fun ọ, iwọ o si ma jẹ eweko igbẹ: 19 Li õgùn oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ. 20 Adamu si pè orukọ aya rẹ̀ ni Efa; nitori on ni iṣe iya alãye gbogbo. 21 Ati fun Adamu ati fun aya rẹ̀ li OLUWA Ọlọrun da ẹwu awọ, o si fi wọ̀ wọn.

Ọlọrun Lé Adamu ati Efa jáde ninu Ọgbà

22 OLUWA Ọlọrun si wipe, Wò o, ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ̀ rere ati bururu: njẹ nisisiyi ki o má ba nà ọwọ́ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi ìye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yè titi lai; 23 Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá. 24 Bẹ̃li o lé ọkunrin na jade; o si fi awọn kerubu ati idà ina dè ìha ìla-õrùn Edeni ti njù kakiri, lati ma ṣọ́ ọ̀na igi ìye na.

Genesisi 4

Kaini ati Abeli

1 ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA. 2 O si bí Abeli arakunrin rẹ̀. Abeli a si ma ṣe oluṣọ-agutan, ṣugbọn Kaini a ma ṣe aroko. 3 O si ṣe, li opin ọjọ́ wọnni ti Kaini mu ọrẹ ninu eso ilẹ fun OLUWA wá. 4 Ati Abeli, on pẹlu mu ninu akọbi ẹran-ọ̀sin ani ninu awọn ti o sanra. OLUWA si fi ojurere wò Abeli ati ọrẹ rẹ̀; 5 Ṣugbọn Kaini ati ọrẹ rẹ̀ ni kò nãni. Kaini si binu gidigidi, oju rẹ̀ si rẹ̀wẹsi. 6 OLUWA si bi Kaini pe, Ẽṣe ti inu fi mbi ọ? ẽ si ti ṣe ti oju rẹ̀ fi rẹ̀wẹsi? 7 Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ? bi iwọ kò ba si ṣe rere, ẹ̀ṣẹ ba li ẹnu-ọ̀na, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yio ma fà si, iwọ o si ma ṣe alakoso rẹ̀. 8 Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa. 9 OLUWA si wi fun Kaini pe, Nibo ni Abeli arakunrin rẹ wà? O si wipe, Emi kò mọ̀; emi iṣe olutọju arakunrin mi bi? 10 O si wipe, Kini iwọ ṣe nì? Ohùn ẹ̀jẹ arakunrin rẹ nkigbe pè mi lati inu ilẹ wá. 11 Njẹ nisisiyi a fi ọ ré lori ilẹ, ti o yanu rẹ̀ gbà ẹ̀jẹ arakunrin rẹ lọwọ rẹ. 12 Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye. 13 Kaini si wi fun OLUWA pe, ìya ẹ̀ṣẹ mi pọ̀ jù eyiti emi lè rù lọ. 14 Kiye si i, iwọ lé mi jade loni kuro lori ilẹ; emi o si di ẹniti o pamọ kuro loju rẹ; emi o si ma jẹ isansa ati alarinkiri li aiye; yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ri mi yio lù mi pa. 15 OLUWA si wi fun u pe, Nitorina ẹnikẹni ti o ba pa Kaini a o gbẹsan lara rẹ̀ lẹrinmeje. OLUWA si sàmi si Kaini lara, nitori ẹniti o ba ri i ki o má ba pa a. 16 Kaini si jade lọ kuro niwaju OLUWA, o si joko ni ilẹ Nodi, ni ìha ìla-õrùn Edeni.

Àwọn Ìran Kaini

17 Kaini si mọ̀ aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Enoku: o si tẹ̀ ilu kan dó, o si sọ orukọ ilu na ni Enoku bi orukọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin. 18 Fun Enoku li a bí Iradi: Iradi si bí Mehujaeli: Mehujaeli si bí Metuṣaeli: Metuṣaeli si bí Lameki. 19 Lameki si fẹ́ obinrin meji: orukọ ekini ni Ada, ati orukọ ekeji ni Silla. 20 Ada si bí Jabali: on ni baba irú awọn ti o ngbé agọ́, ti nwọn si li ẹran-ọ̀sin. 21 Orukọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali: on ni baba irú gbogbo awọn ti nlò dùru ati fère. 22 Ati Silla on pẹlu bí Tubali-kaini, olukọni gbogbo ọlọnà idẹ, ati irin: arabinrin Tubali-kaini ni Naama. 23 Lameki si wi fun awọn aya rẹ̀ pe, Ada on Silla, ẹ gbọ́ ohùn mi; ẹnyin aya Lameki, ẹ fetisi ọ̀rọ mi: nitoriti mo pa ọkunrin kan si ẹ̀dun mi, ati ọdọmọkunrin kan si ipalara mi. 24 Bi a o gbẹsan Kaini lẹrinmeje, njẹ ti Lameki ni ìgba ãdọrin meje.

Seti ati Enọṣi

25 Adamu si tun mọ̀ aya rẹ̀, o si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: o wipe, nitori Ọlọrun yàn irú-ọmọ miran fun mi ni ipò Abeli ti Kaini pa. 26 Ati Seti, on pẹlu li a bí ọmọkunrin kan fun; o si pè orukọ rẹ̀ ni Enoṣi: nigbana li awọn enia bẹ̀rẹ si ikepè orukọ OLUWA.

Genesisi 5

Ìwé Àkọsílẹ̀ Ìran Adamu

1 EYI ni iwe iran Adamu: Li ọjọ́ ti Ọlọrun dá ọkunrin, li aworan Ọlọrun li o dá a. 2 Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn. 3 Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: 4 Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 5 Gbogbo ọjọ́ ti Adamu wà si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé ọgbọ̀n: o si kú. 6 Seti si wà li ọgọrun ọdún o lé marun, o si bí Enoṣi: 7 Seti si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé meje lẹhin ti o bí Enoṣi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 8 Ati gbogbo ọjọ́ Seti jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdun o lé mejila: o si kú. 9 Enoṣi si wà li ãdọrun ọdún, o si bí Kenani: 10 Enoṣi si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé mẹ̃dogun lẹhin ti o bí Kenani, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 11 Gbogbo ọjọ́ Enoṣi si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé marun: o si kú. 12 Kenani si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Mahalaleli: 13 Kenani si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ogoji lẹhin ti o bí Mahalaleli, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 14 Gbogbo ọjọ́ Kenani si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé mẹwa: o si kú. 15 Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi: 16 Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 17 Gbogbo ọjọ́ Mahalaleli si jẹ ẹ̃dẹgbẹ̀run ọdún o dí marun: o si kú. 18 Jaredi si wà li ọgọjọ ọdún o lé meji, o si bí Enoku: 19 Jaredi si wà li ẹgbẹrin ọdún lẹhin igbati o bì Enoku, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 20 Gbogbo ọjọ́ Jaredi si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mejidilogoji: o si kú. 21 Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela: 22 Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 23 Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji: 24 Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ. 25 Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki: 26 Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 27 Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú. 28 Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan: 29 O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú. 30 Lameki si wà li ẹgbẹta ọdún o dí marun, lẹhin ti o bí Noa, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 31 Gbogbo ọjọ́ Lameki si jẹ ẹgbẹrin ọdún o dí mẹtalelogun: o si kú. 32 Noa si jẹ ẹni ẹ̃dẹgbẹta ọdún: Noa si bí Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.

Genesisi 6

Ìwà Burúkú Eniyan

1 O si ṣe nigbati enia bẹ̀rẹ si irẹ̀ lori ilẹ, ti a si bí ọmọbinrin fun wọn, 2 Ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbinrin enia pe, nwọn lẹwà; nwọn fẹ́ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yàn. 3 OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún. 4 Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí. 5 Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ. 6 Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀. 7 OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn. 8 Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.

Ìtàn Noa

9 Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn. 10 Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti. 11 Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara. 12 Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye. 13 Ọlọrun si wi fun Noa pe, Opin gbogbo enia de iwaju mi; nitori ti aiye kún fun ìwa-agbara lati ọwọ́ wọn; si kiye si i, emi o si pa wọn run pẹlu aiye. 14 Iwọ fi igi goferi kàn ọkọ́ kan; ikele-ikele ni iwọ o ṣe ninu ọkọ́ na, iwọ o si fi ọ̀da kùn u ninu ati lode. 15 Bayi ni iwọ o si ṣe e: Ìna ọkọ̀ na yio jẹ ọ̃dunrun igbọ́nwọ, ìbú rẹ̀ ãdọta igbọ́nwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọ̀nwọ. 16 Ferese ni iwọ o si ṣe si ọkọ̀ na ni igbọ́nwọ kan ni ki iwọ ki o si pari wọn loke; lẹgbẹ ni iwọ o si dá ẹnu-ọ̀na ọkọ̀ na, si: pẹlu yara isalẹ, atẹle, ati ẹkẹta loke ni iwọ o ṣe e. 17 Ati emi, wò o, emi nmu kikun-omi bọ̀ wá si aiye, lati pa gbogbo ohun alãye run, ti o li ẹmi ãye ninu kuro labẹ ọrun; ohun gbogbo ti o wà li aiye ni yio si kú. 18 Ṣugbọn iwọ li emi o ba dá majẹmu mi; iwọ o si wọ̀ inu ọkọ̀ na, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati aya rẹ, ati awọn aya awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ. 19 Ati ninu ẹdá alãye gbogbo, ninu onirũru ẹran, meji meji ninu gbogbo ẹran ni iwọ o mu wọ̀ inu ọkọ̀ na, lati mu nwọn là pẹlu rẹ; ti akọ ti abo ni ki nwọn ki o jẹ. 20 Ninu ẹiyẹ nipa irú ti wọn, ninu ẹran-ọ̀sin nipa irú ti wọn, ninu ohun gbogbo ti nrakò ni ilẹ nipa irú tirẹ̀, meji meji ninu gbogbo wọn ni yio ma tọ̀ ọ wá lati mu wọn wà lãye. 21 Iwọ o si mu ninu ohun jijẹ gbogbo, iwọ o si kó wọn jọ si ọdọ rẹ; yio si ṣe onjẹ fun iwọ, ati fun wọn. 22 Bẹ̃ni Noa si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ọlọrun paṣẹ fun u, bẹli o ṣe.

Genesisi 7

Ìkún Omi

1 OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi. 2 Ninu onirũru ẹran ti o mọ́ meje meje ni ki iwọ ki o mu wọn, ati akọ ati abo rẹ̀; ati ninu ẹran ti kò mọ́ meji meji, ati akọ ati abo rẹ̀. 3 Ninu ẹiyẹ oju-ọrun pẹlu ni meje meje, ati akọ ati abo; lati dá irú si lãye lori ilẹ gbogbo. 4 Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ. 5 Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u. 6 Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye. 7 Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi. 8 Ninu ẹranko mimọ́, ati ninu ẹranko ti kò mọ́, ati ninu ẹiyẹ, ati ninu ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, 9 Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa. 10 O si ṣe ni ijọ́ keje, bẹ̃ni kíkun-omi de si aiye. 11 Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadilogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ. 12 Òjo na si wà lori ilẹ li ogoji ọsán on ogoji oru. 13 Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn). 14 Awọn, ati gbogbo ẹranko ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin gbogbo ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ nla ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ abiyẹ. 15 Nwọn si wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀, meji meji ninu ẹda gbogbo, ninu eyiti ẹmi ìye wà. 16 Awọn ti o si wọle lọ, nwọn wọle ti akọ ti abo ninu ẹdá gbogbo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. OLUWA si sé e mọ́ ile. 17 Ikún-omi si wà li ogoji ọjọ́ lori ilẹ; omi si nwú si i, o si mu ọkọ̀ fó soke, o si gbera kuro lori ilẹ. 18 Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi. 19 Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ. 20 Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ. 21 Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia: 22 Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú. 23 Ohun alãye gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. 24 Omi si gbilẹ li aiye li ãdọjọ ọjọ́.

Genesisi 8

Ìkún Omi Gbẹ

1 ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà. 2 A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá. 3 Omi si npada kuro lori ilẹ, lojojumọ lẹhin ãdọjọ ọjọ́, omi si fà. 4 Ọkọ̀ si kanlẹ li oṣù keje, ni ijọ́ kẹtadilogun oṣù, lori oke Ararati. 5 Omi si nfà titi o fi di oṣù kẹwa: li oṣù kẹwa, li ọjọ́ kini oṣù li ori awọn okenla hàn, 6 O si ṣe li opin ogoji ọjọ́, ni Noa ṣí ferese ọkọ̀ ti o kàn: 7 O si rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ ka kiri titi omi fi gbẹ kuro lori ilẹ. 8 O si rán oriri kan jade, lati ọdọ rẹ̀ lọ, ki o wò bi omi ba nfà kuro lori ilẹ; 9 Ṣugbọn oriri kò ri ibi isimi fun atẹlẹsẹ̀ rẹ̀, o si pada tọ ọ lọ ninu ọkọ̀, nitoriti omi wà lori ilẹ gbogbo: nigbana li o si nawọ rẹ̀, o mu u, o si fà a si ọdọ rẹ̀ ninu ọkọ̀. 10 O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ. 11 Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ. 12 O si tun duro ni ijọ́ meje miran, o si rán oriri na jade; ti kò si tun pada tọ̀ ọ wá mọ́. 13 O si ṣe li ọdún kọkanlelẹgbẹta, li oṣù kini, li ọjọ́ kini oṣù na, on li omi gbẹ kuro lori ilẹ: Noa si ṣí ideri ọkọ̀, o si wò, si kiyesi i ori ilẹ gbẹ. 14 Li oṣù keji, ni ijọ́ kẹtadilọgbọ̀n oṣù, on ni ilẹ gbẹ. 15 Ọlọrun si sọ fun Noa pe, 16 Jade kuro ninu ọkọ̀, iwọ, ati aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn aya ọmọ rẹ pẹlu rẹ. 17 Mu ohun alãye gbogbo ti o wà pẹlu rẹ jade pẹlu rẹ, ninu ẹdá gbogbo, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ; ki nwọn ki o le ma gbá yìn lori ilẹ, ki nwọn bí si i, ki nwọn si ma rẹ̀ si i lori ilẹ. 18 Noa si jade, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati awọn aya ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; 19 Gbogbo ẹranko, gbogbo ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ gbogbo, ati ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, gẹgẹ bi irú ti wọn, nwọn jade ninu ọkọ̀.

Noa Rúbọ

20 Noa si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA; o si mu ninu ẹranko mimọ́ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ́ gbogbo, o si rú ẹbọ-ọrẹ sisun lori pẹpẹ na. 21 OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe. 22 Niwọ̀n ìgba ti aiye yio wà, ìgba irugbìn, ati ìgba ikore, ìgba otutu ati oru, ìgba ẹ̃run on òjo, ati ọsán ati oru, ki yio dẹkun.

Genesisi 9

Ọlọrun Bá Noa Dá Majẹmu

1 ỌLỌRUN si sure fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ ma bí si i, ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si kún aiye. 2 Ati ìbẹru nyin, ati ìfoya nyin, yio ma wà lara gbogbo ẹranko aiye, ati lara gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati lara gbogbo ohun ti nrakò ni ilẹ, ati lara gbogbo ẹja okun; ọwọ́ nyin li a fi wọn lé. 3 Gbogbo ohun alãye, ti nrakò, ni yio ma ṣe onjẹ fun nyin; gẹgẹ bi eweko tutu ni mo fi ohun gbogbo fun nyin. 4 Kìki ẹran pẹlu ẹmi rẹ̀, ani ẹ̀jẹ rẹ̀, on li ẹnyin kò gbọdọ jẹ. 5 Nitõtọ ẹ̀jẹ nyin ani ẹmi nyin li emi o si bère; lọwọ gbogbo ẹranko li emi o bère rẹ̀, ati lọwọ enia, lọwọ arakunrin olukuluku enia li emi o bère ẹmi enia. 6 Ẹnikẹni ti o ba ta ẹ̀jẹ enia silẹ, lati ọwọ́ enia li a o si ta ẹ̀jẹ rẹ̀ silẹ: nitoripe li aworan Ọlọrun li o dá enia. 7 Ati ẹnyin, ki ẹnyin ki o ma bí si i; ki ẹ si ma rẹ̀ si i, ki ẹ si ma gbá yìn lori ilẹ, ki ẹ si ma rẹ̀ ninu rẹ̀. 8 Ọlọrun si wi fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, pe, 9 Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin; 10 Ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin; ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ẹranko aiye pélu nyin; lati gbogbo awọn ti o ti inu ọkọ̀ jade, titi o fi de gbogbo ẹranko aiye. 11 Emi o si ba nyin dá majẹmu mi; a ki yio si fi kíkun-omi ké gbogbo ẹdá kuro mọ́; bẹ̃ni kíkun-omi ki yio sí mọ́, lati pa aiye run. 12 Ọlọrun si wipe, Eyiyi li àmi majẹmu mi ti mo ba nyin dá, ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin, fun atirandiran: 13 Mo fi òṣumare mi si awọsanma, on ni yio si ma ṣe àmi majẹmu mi ti mo ba aiye dá. 14 Yio si ṣe, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òṣumare na li awọsanma: 15 Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹnyin, ati gbogbo ọkàn alãye ni gbogbo ẹdá; omi ki yio si di kíkun mọ́ lati pa gbogbo ẹdá run. 16 Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye. 17 Ọlọrun si wi fun Noa pe, Eyiyi li àmi majẹmu na, ti mo ba ara mi ati ẹdá gbogbo ti o wà lori ilẹ dá.

Noa ati Àwọn Ọmọkunrin Rẹ̀

18 Awọn ọmọ Noa, ti o si jade ninu ọkọ̀ ni Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti: Hamu si ni baba Kenaani. 19 Awọn mẹta wọnyi li ọmọ Noa: lati ọdọ wọn li a gbé ti tàn ká gbogbo aiye. 20 Noa si bẹ̀rẹ si iṣe àgbẹ, o si gbìn ọgbà-àjara: 21 O si mu ninu ọti-waini na, o mu amupara; o si tú ara rẹ̀ si ìhoho ninu agọ́ rẹ̀. 22 Hamu, baba Kenaani, si ri ìhoho baba rẹ̀, o si sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ meji lode. 23 Ati Ṣemu ati Jafeti mu gọgọwu, nwọn si fi le ejika awọn mejeji, nwọn si fi ẹhin rìn, nwọn si bò ìhoho baba wọn; oju wọn si wà lẹhin; nwọn kò si ri ìhoho baba wọn. 24 Noa si jí kuro li oju ọti-waini rẹ̀, o si mọ̀ ohun ti ọmọ rẹ̀ kekere ṣe si i. 25 O si wipe, Egbe ni fun Kenaani; iranṣẹ awọn iranṣẹ ni yio ma ṣe fun awọn arakunrin rẹ̀. 26 O si wipe, Olubukun li OLUWA Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio ma ṣe iranṣẹ rẹ̀. 27 Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ́ Ṣemu; Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn. 28 Noa si wà ni irinwo ọdun o din ãdọta, lẹhin ìkún-omi. 29 Gbogbo ọjọ́ Noa jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí ãdọta: o si kú.

Genesisi 10

Ìran Àwọn Ọmọ Noa

1 IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi. 2 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi. 3 Ati awọn ọmọ Gomeri, Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma. 4 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu. 5 Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pín erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ̀; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn. 6 Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani. 7 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka; ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani. 8 Kuṣi si bí Nimrodu: on si bẹ̀rẹ si idi alagbara li aiye. 9 On si ṣe ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA: nitori na li a ṣe nwipe, Gẹgẹ bi Nimrodu ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA. 10 Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari. 11 Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó. 12 Ati Reseni lagbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla. 13 Misraimu si bí Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu, 14 Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu. 15 Kenaani si bí Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti, 16 Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi, 17 Ati awọn ara Hiffi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini, 18 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati; lẹhin eyini ni idile awọn ara Kenaani tàn kalẹ. 19 Ati àgbegbe awọn ara Kenaani ni Sidoni, bi o ti mbọ̀wa Gerari, titi de Gasa; bi o ti nlọ si Sodomu, ati Gomorra, ati Adma, ati Seboimu, titi dé Laṣa. 20 Awọn wọnyi li ọmọ Hamu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, ati li orilẹ-ède wọn. 21 Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ. 22 Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu. 23 Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi. 24 Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi. 25 Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani. 26 Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera, 27 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla, 28 Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba, 29 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu: gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Joktani. 30 Ibugbe wọn si ti Meṣa lọ, bi iwọ ti nlọ si Sefari, oke kan ni ìla-õrùn. 31 Awọn wọnyi li ọmọ Ṣemu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, li orilẹ-ède wọn. 32 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Noa, gẹgẹ bi iran wọn, li orilẹ-ède wọn: lati ọwọ́ awọn wọnyi wá li a ti pín orilẹ-ède aiye lẹhin kíkun-omi.

Genesisi 11

Ilé Ìṣọ́ Babeli

1 GBOGBO aiye si jẹ ède kan, ati ọ̀rọ kan. 2 O si ṣe, bi nwọn ti nrìn lati ìha ìla-õrùn lọ, ti nwọn ri pẹtẹlẹ kan ni ilẹ Ṣinari; nwọn si tẹdo sibẹ̀. 3 Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ. 4 Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo. 5 OLUWA si sọkalẹ wá iwò ilu ati ile-iṣọ́ na, ti awọn ọmọ enia nkọ́. 6 OLUWA si wipe, Kiye si i, ọkan li awọn enia, ède kan ni gbogbo wọn ni; eyi ni nwọn bẹ̀rẹ si iṣe: njẹ nisisiyi kò sí ohun ti a o le igbà lọwọ wọn ti nwọn ti rò lati ṣe. 7 Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́. 8 Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó. 9 Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.

Àwọn Ìran Ṣemu

10 Wọnyi ni iran Ṣemu: Ṣemu jẹ ẹni ọgọrun ọdún, o si bí Arfaksadi li ọdún keji lẹhin kíkun-omi. 11 Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 12 Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela: 13 Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 14 Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi: 15 Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 16 Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi: 17 Eberi si wà ni irinwo ọdún o le ọgbọ̀n lẹhin igbati o bí Pelegi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 18 Pelegi si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bì Reu: 19 Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 20 Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu: 21 Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 22 Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori: 23 Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 24 Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkanlelọgbọ̀n o si bí Tera: 25 Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 26 Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani.

Àwọn Ìran Tẹra

27 Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti. 28 Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea. 29 Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska. 30 Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ. 31 Tera si mu Abramu ọmọ rẹ̀, ati Loti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ati Sarai aya ọmọ rẹ̀, aya Abramu ọmọ rẹ̀; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ̀. 32 Ọjọ́ Tera si jẹ igba ọdún o le marun: Tera si kú ni Harani.

Genesisi 12

Ọlọrun Pe Abramu

1 OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ: 2 Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi: 3 Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye. 4 Bẹ̃li Abramu lọ, bi OLUWA ti sọ fun u; Loti si ba a lọ: Abramu si jẹ ẹni arundilọgọrin ọdún nigbati o jade ni Harani. 5 Abramu si mu Sarai aya rẹ̀, ati Loti ọmọ arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ini wọn ti nwọn kojọ, enia gbogbo ti nwọn ni ni Harani, nwọn si jade lati lọ si ilẹ Kenaani; ni ilẹ Kenaani ni nwọn si wá si. 6 Abramu si là ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npè ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni ìgba na. 7 OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a. 8 O si ṣí kuro nibẹ̀ lọ si ori oke kan ni ìha ìla-õrùn Beteli, o si pa agọ́ rẹ̀, Beteli ni ìwọ-õrùn ati Hai ni ìla-õrùn: o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA. 9 Abramu si nrìn lọ, o nlọ si ìha gusù sibẹ̀.

Abramu ní Ijipti

10 Ìyan kan si mu ni ilẹ na: Abramu si sọkalẹ lọ si Egipti lati ṣe atipo nibẹ̀; nitoriti ìyan na mu gidigidi ni ilẹ na. 11 O si ṣe, nigbati o kù si dẹ̀dẹ lati wọ̀ Egipti, o wi fun Sarai aya rẹ̀ pe, Kiyesi i nisisiyi, emi mọ̀ pe arẹwà obinrin lati wò ni iwọ: 12 Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si. 13 Mo bẹ̀ ọ, wipe, arabinrin mi ni iwọ iṣe: ki o le irọ̀ mi lọrùn nitori rẹ; ọkàn mi yio si yè nitori rẹ. 14 O si ṣe nigbati Abramu de Egipti, awọn ara Egipti wò obinrin na pe arẹwà enia gidigidi ni. 15 Awọn ijoye Farao pẹlu ri i, nwọn si ròhin rẹ̀ niwaju Farao; a si mu obinrin na lọ si ile Farao. 16 O si nṣikẹ Abramu gidigidi nitori rẹ̀: on si li agutan, ati akọ-malu, ati akọ-kẹtẹkẹtẹ, ati iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, abo-kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ. 17 OLUWA si fi iyọnu nla yọ Farao ati awọn ara ile rẹ̀ li ẹnu, nitori Sarai aya Abramu. 18 Farao si pè Abramu, o wipe, ewo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? ẽṣe ti iwọ kò fi wi fun mi pe, aya rẹ ni iṣe? 19 Ẽṣe ti iwọ fi wipe, arabinrin mi ni iṣe? bẹ̃li emi iba fẹ ẹ li aya mi si: njẹ nisisiyi wò aya rẹ, mu u, ki o si ma ba tirẹ lọ. 20 Farao si paṣẹ fun awọn ọkunrin rẹ̀ nitori Abramu: nwọn si sìn i jade lọ, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni.

Genesisi 13

Abramu ati Lọti Pínyà

1 ABRAMU si goke lati Egipti wá, on, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ati Loti pẹlu rẹ̀, si ìha gusu. 2 Abramu si là gidigidi, li ẹran-ọ̀sin, ni fadaka, ati ni wurà. 3 O si nrìn ìrin rẹ̀ lati ìha gusu lọ titi o si fi de Beteli, de ibi ti agọ́ rẹ̀ ti wà ni iṣaju, lagbedemeji Beteli on Hai. 4 Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA. 5 Ati Loti pẹlu, ti o ba Abramu lọ, ni agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran, ati agọ́. 6 Ilẹ na kò si le igbà wọn, ki nwọn ki o le igbé pọ̀: nitori ini wọn pọ̀, bẹ̃nì nwọn kò si le gbé pọ̀. 7 Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na. 8 Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe. 9 Gbogbo ilẹ kọ́ eyi niwaju rẹ? emi bẹ̀ ọ, yà ara rẹ kuro lọdọ mi: bi iwọ ba pọ̀ si apa òsi, njẹ emi o pọ̀ si ọtún; tabi bi iwọ ba pọ̀ si apa ọtùn, njẹ emi o pọ̀ si òsi. 10 Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari. 11 Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji. 12 Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu. 13 Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu ṣe enia buburu, ati ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju OLUWA.

Abramu kó Lọ sí Heburoni

14 OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Loti yà kuro lọdọ rẹ̀ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà nì lọ, si ìha ariwa, ati si ìha gusu, si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ìwọ-õrùn: 15 Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai. 16 Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu. 17 Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun. 18 Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.

Genesisi 14

Abramu Gba Lọti sílẹ̀

1 O SI ṣe li ọjọ́ Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu, ati Tidali ọba awọn orilẹ-ède; 2 Ti nwọn ba Bera ọba Sodomu jagun, pẹlu Birṣa ọba Gomorra, Ṣinabu ọba Adma, ati Semeberi ọba Seboimu, pẹlu ọba Bela (eyini ni Soari). 3 Gbogbo awọn wọnyi li o dapọ̀ li afonifoji Siddimu, ti iṣe Okun Iyọ̀. 4 Nwọn sìn Kedorlaomeri li ọdún mejila, li ọdún kẹtala nwọn ṣọ̀tẹ. 5 Li ọdún kẹrinla ni Kedorlaomeri, wá ati awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn kọlu awọn Refaimu ni Aṣteroti-Karnaimu, ati awọn Susimu ni Hamu, ati awọn Emimu ni pẹtẹlẹ Kiriataimu, 6 Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù. 7 Nwọn si pada, nwọn si wá si Enmiṣpati, eyini ni Kadeṣi, nwọn si kọlu gbogbo oko awọn ara Amaleki, ati awọn ara Amori ti o tẹdo ni Hasesontamari pẹlu. 8 Ọba Sodomu si jade, ati ọba Gomorra, ati ọba Adma, ati ọba Seboimu, ati ọba Bela, (eyini ni Soari;) nwọn si tẹgun si ara wọn li afonifoji Siddimu; 9 Si Kedorlaomeri ọba Elamu, ati si Tidali ọba awọn orilẹ-ède, ati Amrafeli ọba Ṣinari, ati Arioku ọba Ellasari, ọba mẹrin si marun. 10 Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke. 11 Nwọn si kó gbogbo ẹrù Sodomu on Gomorra ati gbogbo onjẹ wọn, nwọn si ba ti wọn lọ. 12 Nwọn si mu Loti, ọmọ arakunrin Abramu, ti ngbé Sodomu, nwọn si kó ẹrù rẹ̀, nwọn si lọ. 13 Ẹnikan ti o sá asalà de, o si rò fun Abramu Heberu nì; on sa tẹdo ni igbo Mamre ara Amori, arakunrin Eṣkoli ati arakunrin Aneri: awọn wọnyi li o mba Abramu ṣe pọ̀. 14 Nigbati Abramu gbọ́ pe a dì arakunrin on ni igbekun, o kó awọn ọmọ ọdọ rẹ̀ ti a ti kọ́, ti a bí ni ile rẹ̀ jade, ọrindinirinwo enia o din meji, o si lepa wọn de Dani. 15 O si pín ara rẹ̀, on, pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, si wọn li oru, o si kọlù wọn, o si lépa wọn de Hoba, ti o wà li apa òsi Damasku: 16 O si gbà gbogbo ẹrù na pada, o si gbà Loti arakunrin rẹ̀ pada pẹlu, ati ẹrù rẹ̀, ati awọn obinrin pẹlu, ati awọn enia.

Mẹlikisẹdẹki Súre fún Abramu

17 Ọba Sodomu si jade lọ ipade rẹ̀ li àbọ iṣẹgun Kedorlaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ̀, li afonifoji Ṣafe, ti iṣe Afonifoji Ọba. 18 Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wá: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo. 19 O si súre fun u, o si wipe, Ibukun ni fun Abramu, ti Ọlọrun ọga-ogo, ẹniti o ni ọrun on aiye. 20 Olubukun si li Ọlọrun ọga-ogo ti o fi awọn ọta rẹ le ọ lọwọ. On si dá idamẹwa ohun gbogbo fun u. 21 Ọba Sodomu si wi fun Abramu pe, Dá awọn enia fun mi, ki o si mu ẹrù fun ara rẹ. 22 Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, Mo ti gbé ọwọ́ mi soke si OLUWA, Ọlọrun ọga-ogo, ti o ni ọrun on aiye, 23 Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀: 24 Bikoṣe kìki eyiti awọn ọdọmọkunrin ti jẹ, ati ipín ti awọn ọkunrin ti o ba mi lọ; Aneri, Eṣkoli, ati Mamre; jẹ ki nwọn ki o mu ipín ti wọn.

Genesisi 15

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Abramu

1 LẸHIN nkan wọnyi ọ̀rọ OLUWA tọ̀ Abramu wá li ojuran, wipe, Má bẹ̀ru, Abramu; Emi li asà rẹ, ère nla rẹ gidigidi. 2 Abramu si wipe, OLUWA Ọlọrun, kini iwọ o fi fun mi, emi sa nlọ li ailọmọ, Elieseri ti Damasku yi si ni ẹniti o ni ile mi? 3 Abramu si wipe, Wo o emi ni iwọ kò fi irú-ọmọ fun: si wo o, ẹrú ti a bi ni ile mi ni yio jẹ arolé. 4 Si wo o, ọ̀rọ OLUWA tọ̀ ọ wá, wipe, Eleyi ki yio ṣe arole rẹ; bikoṣe ẹniti yio ti inu ara rẹ jade, on ni yio ṣe arole rẹ. 5 O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹ̃ni irú-ọmọ rẹ yio ri. 6 O si gba OLUWA gbọ́; on si kà a si fun u li ododo. 7 O si wi fun u pe, Emi li OLUWA ti o mu ọ jade lati Uri ti Kaldea wá, lati fi ilẹ yi fun ọ lati jogun rẹ̀. 8 O si wipe, OLUWA Ọlọrun, nipa bawo li emi o fi mọ̀ pe emi o jogun rẹ̀? 9 O si wi fun u pe, Mu ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta fun mi wá, ati ewurẹ ọlọdun mẹta, ati àgbo ọlọdun mẹta, ati oriri kan, ati ọmọ ẹiyẹle kan. 10 O si mu gbogbo nkan wọnyi wá sọdọ rẹ̀, o si là wọn li agbedemeji, o si fi ẹ̀la ekini kọju si ekeji: bikoṣe awọn ẹiyẹ ni kò là. 11 Nigbati awọn ẹiyẹ si sọkalẹ wá si ori okú wọnyi, Abramu lé wọn kuro. 12 O si ṣe nigbati õrùn nwọ̀ lọ, orun ìjika kùn Abramu; si kiyesi i, ẹ̀ru bà a, òkunkun biribiri si bò o. 13 On si wi fun Abramu pe, Mọ̀ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni íya ni irinwo ọdún; 14 Ati orilẹ-ède na pẹlu ti nwọn o ma sìn, li emi o dá lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade ti awọn ti ọrọ̀ pipọ̀. 15 Iwọ o si tọ̀ awọn baba rẹ lọ li alafia; li ogbologbo ọjọ́ li a o sin ọ. 16 Ṣugbọn ni iran kẹrin, nwọn o si tun pada wá nihinyi: nitori ẹ̀ṣẹ awọn ara Amori kò ti ikún. 17 O si ṣe nigbati õrùn wọ̀, òkunkun si ṣú, kiyesi i ileru elẽfin, ati iná fitila ti nkọja lãrin ẹ̀la wọnni. 18 Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate: 19 Awọn enia Keni, ati awọn enia Kenissi, ati awọn enia Kadmoni, 20 Ati awọn enia Hitti, ati awọn enia Perissi, ati awọn Refaimu, 21 Ati awọn enia Amori, ati awọn enia Kenaani, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Jebusi.

Genesisi 16

Hagari ati Iṣimaeli

1 SARAI, aya Abramu, kò bímọ fun u: ṣugbọn o li ọmọ-ọdọ kan obinrin, ara Egipti, orukọ ẹniti ijẹ Hagari. 2 Sarai si wi fun Abramu pe, kiyesi i na, OLUWA dá mi duro lati bímọ: emi bẹ̀ ọ, wọle tọ̀ ọmọbinrin ọdọ mi; o le ṣepe bọya emi a ti ipasẹ rẹ̀ li ọmọ. Abramu si gbà ohùn Sarai gbọ́. 3 Sarai, aya Abramu, si mu Hagari ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ ara Egipti na, lẹhin igbati Abramu gbé ilẹ Kenaani li ọdún mẹwa, o si fi i fun Abramu ọkọ rẹ̀ lati ma ṣe aya rẹ̀. 4 On si wọle tọ̀ Hagari, o si loyun: nigbati o ri pe on loyun, oluwa rẹ̀ obinrin wa di ẹ̀gan li oju rẹ̀. 5 Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ. 6 Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀. 7 Angeli OLUWA si ri i li ẹba isun omi ni ijù, li ẹba isun omi li ọ̀na Ṣuri. 8 O si wipe, Hagari ọmọbinrin ọdọ Sarai, nibo ni iwọ ti mbọ̀? nibo ni iwọ si nrè? O si wipe, emi sá kuro niwaju Sarai oluwa mi. 9 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Pada, lọ si ọdọ oluwa rẹ, ki o si tẹriba fun u. 10 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ni bíbi emi o mu iru-ọmọ rẹ bísi i, a ki yio si le kà wọn fun ọ̀pọlọpọ. 11 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, kiyesi i iwọ loyun, iwọ o si bí ọmọkunrin, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Iṣmaeli; nitoriti OLUWA ti gbọ́ ohùn arò rẹ. 12 Jagidijagan enia ni yio si ṣe; ọwọ́ rẹ̀ yio wà lara enia gbogbo, ọwọ́ enia gbogbo yio si wà lara rẹ̀: on o si ma gbé iwaju gbogbo awọn arakunrin rẹ̀. 13 O si pè orukọ OLUWA ti o ba a sọ̀rọ ni, Iwọ Ọlọrun ti o ri mi: nitori ti o wipe, Emi ha wá ẹniti o ri mi kiri nihin? 14 Nitori na li a ṣe npè kanga na ni Beer-lahai-roi: kiyesi i, o wà li agbedemeji Kadeṣi on Beredi. 15 Hagari si bí ọmọkunrin kan fun Abramu: Abramu si pè orukọ ọmọ ti Hagari bí ni Iṣmaeli. 16 Abramu si jẹ ẹni ẹrindilãdọrun ọdún, nigbati Hagari bí Iṣmaeli fun Abramu.

Genesisi 17

Ilà Abẹ́ Kíkọ, Àmì Majẹmu Ọlọrun

1 NIGBATI Abramu si di ẹni ọkandilọgọrun ọdún, OLUWA farahàn Abramu, o si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare; mã rìn niwaju mi, ki iwọ ki o si pé. 2 Emi o si ba ọ dá majẹmu mi, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi. 3 Abramu si dojubolẹ; Ọlọrun si ba a sọ̀rọ pe, 4 Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ̀. 5 Bẹ̃li a ki yio si pe orukọ rẹ ni Abramu mọ́, bikoṣe Abrahamu li orukọ rẹ yio jẹ; nitoriti mo ti sọ ọ di baba orilẹ-ède pupọ̀. 6 Emi o si mu ọ bí si i pupọpupọ, ọ̀pọ orilẹ-ède li emi o si mu ti ọdọ rẹ wá, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wá. 7 Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lãrin temi tirẹ, ati lãrin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati ma ṣe Ọlọrun rẹ, ati ti irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ. 8 Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn. 9 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Nitorina ki iwọ ki o ma pa majẹmu mi mọ́, iwọ, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn. 10 Eyi ni majẹmu mi, ti ẹnyin o ma pamọ́ lãrin temi ti nyin, ati lãrin irú-ọmọ rẹ, lẹhin rẹ; gbogbo ọmọkunrin inu nyin li a o kọ ni ilà. 11 Ẹnyin o si kọ ara nyin ni ilà; on ni yio si ṣe àmi majẹmu lãrin temi ti nyin. 12 Ẹniti o ba si di ọmọkunrin ijọ mẹjọ ninu nyin li a o kọ ni ilà, gbogbo ọmọkunrin ni iran-iran nyin, ati ẹniti a bí ni ile, tabi ti a fi owo rà lọwọ alejo, ti ki iṣe irú-ọmọ rẹ. 13 Ẹniti a bí ni ile rẹ, ati ẹniti a fi owo rẹ rà, a kò le ṣe alaikọ ọ ni ilà: bẹ̃ni majẹmu mi yio si wà li ara nyin ni majẹmu aiyeraiye. 14 Ati ọmọkunrin alaikọlà ti a kò kọ ni ilà ara rẹ̀, ọkàn na li a o si ké kuro ninu awọn enia rẹ̀, o dà majẹmu mi. 15 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Bi o ṣe ti Sarai, aya rẹ nì, iwọ ki yio pè orukọ rẹ̀ ni Sarai mọ́, bikoṣe Sara li orukọ rẹ̀ yio ma jẹ. 16 Emi o si busi i fun u, emi o si bùn ọ li ọmọkunrin kan pẹlu lati ọdọ rẹ̀ wá, bẹ̃li emi o si busi i fun u, on o si ṣe iya ọ̀pọ orilẹ-ède; awọn ọba enia ni yio ti ọdọ rẹ̀ wá. 17 Nigbana li Abrahamu dojubolẹ, o si rẹrin, o si wi li ọkàn rẹ̀ pe, A o ha bímọ fun ẹni ọgọrun ọdún? Sara ti iṣe ẹni ãdọrun ọdún yio ha bímọ bi? 18 Abrahamu si wi fun Ọlọrun pe, Ki Iṣmaeli ki o wà lãye niwaju rẹ! 19 Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀. 20 Emi si ti gbọ́ adura rẹ fun Iṣmaeli: kiyesi i, emi o si busi i fun u, emi o si mu u bisi i, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi; ijoye mejila ni on o bí, emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla: 21 Ṣugbọn majẹmu mi li emi o ba Isaaki dá, ẹniti Sara yio bí fun ọ li akoko iwoyi amọ́dun. 22 O si fi i silẹ li ọ̀rọ iba a sọ, Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ Abrahamu. 23 Abrahamu si mu Iṣmaeli, ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin ti a bí ni ile rẹ̀, ati gbogbo awọn ti a fi owo rẹ̀ rà, gbogbo ẹniti iṣe ọkunrin ninu awọn enia ile Abrahamu; o si kọ wọn ni ilà ara li ọjọ́ na gan, bi Ọlọrun ti sọ fun u. 24 Abrahamu si jẹ ẹni ọkandilọgọrun ọdún, nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀. 25 Ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ ẹni ọdún mẹtala nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀. 26 Li ọjọ́ na gan li a kọ Abrahamu ni ilà, ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin. 27 Ati gbogbo awọn ọkunrin ile rẹ̀, ti a bi ninu ile rẹ̀, ati ti a si fi owo rà lọwọ alejò, ni a kọ ni ilà pẹlu rẹ̀.

Genesisi 18

Ọlọrun Ṣèlérí Ọmọkunrin Kan fún Abrahamu

1 OLUWA si farahàn a ni igbo Mamre: on si joko li ẹnu-ọ̀na agọ́ ni imõru ọjọ́: 2 O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ. 3 O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ: 4 Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi: 5 Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi. 6 Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara. 7 Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e. 8 O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ. 9 Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́. 10 O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na. 11 Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin. 12 Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu? 13 OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán? 14 Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan. 15 Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.

Abrahamu Bẹ̀bẹ̀ fún Sodomu

16 Awọn ọkunrin na si dide kuro nibẹ̀, nwọn kọju sihà Sodomu: Abrahamu si ba wọn lọ lati sìn wọn de ọ̀na. 17 OLUWA si wipe, Emi o ha pa ohun ti emi o ṣe mọ́ fun Abrahamu: 18 Nitori pe, Abrahamu yio sa di orilẹ-ède nla ati alagbara, ati gbogbo orilẹ-ède aiye li a o bukun fun nipasẹ rẹ̀? 19 Nitoriti mo mọ̀ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u. 20 OLUWA si wipe, Nitori ti igbe Sodomu on Gomorra pọ̀, ati nitori ti ẹ̀ṣẹ wọn pàpọju. 21 Emi o sọkalẹ lọ nisisiyi, ki nri bi nwọn tilẹ ṣe, gẹgẹ bi okikí igbe rẹ̀, ti o de ọdọ mi; bi bẹ si kọ, emi o mọ̀. 22 Awọn ọkunrin na si yi oju wọn pada kuro nibẹ̀, nwọn si lọ si Sodomu: ṣugbọn Abrahamu duro sibẹ̀ niwaju OLUWA. 23 Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu? 24 Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀? 25 O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́? 26 OLUWA si wipe, Bi mo ba ri ãdọta olododo ninu ilu Sodomu, njẹ emi o dá gbogbo ibẹ̀ si nitori wọn. 27 Abrahamu si dahùn o si wipe, Wò o nisisiyi, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ, emi ẹniti iṣe erupẹ ati ẽru. 28 Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u. 29 O si tun sọ fun u ẹ̀wẹ, o ni, Bọya, a o ri ogoji nibẹ̀, On si wipe, Emi ki o run u nitori ogoji. 30 O si tun wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, emi o si ma wi: bọya a o ri ọgbọ̀n nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u bi mo ba ri ọgbọ̀n nibẹ̀. 31 O si wipe, Wò o na, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ: bọya a o ri ogun nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori ogun. 32 O si wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, ẹ̃kanṣoṣo yi li emi o si wi mọ. Bọya a o ri mẹwa nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori mẹwa. 33 OLUWA si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna bi o ti ba Abrahamu sọ̀rọ tan; Abrahamu si pada lọ si ibujoko rẹ̀.

Genesisi 19

Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀ Sodomu

1 AWỌN Angeli meji si wá si Sodomu li aṣalẹ; Loti si joko li ẹnu-bode Sodomu: bi Loti si ti ri wọn, o dide lati pade wọn: o si dojubolẹ; 2 O si wipe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnyin oluwa mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ yà si ile ọmọ-ọdọ nyin, ki ẹ si wọ̀, ki ẹ si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ẹnyin o si dide ni kùtukutu, ki ẹ si ma ba ti nyin lọ. Nwọn si wipe, Ndao; ṣugbọn awa o joko ni igboro li oru oni. 3 O si rọ̀ wọn gidigidi; nwọn si yà tọ̀ ọ, nwọn si wọ̀ inu ile rẹ̀; o si sè àse fun wọn, o si dín àkara alaiwu fun wọn, nwọn si jẹ. 4 Ṣugbọn ki nwọn ki o to dubulẹ, awọn ọkunrin ara ilu na, awọn ọkunrin Sodomu, nwọn yi ile na ká, ati àgba ati ewe, gbogbo enia lati ori igun mẹrẹrin wá. 5 Nwọn si pè Loti, nwọn si bi i pe, Nibo li awọn ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá li alẹ yi wà? mu wọn jade fun wa wá, ki awa ki o le mọ̀ wọn. 6 Loti si jade tọ̀ wọn lọ li ẹnu-ọ̀na, o si sé ilẹkun lẹhin rẹ̀. 7 O si wipe, Arakunrin, emi bẹ̀ nyin, ẹ máṣe hùwa buburu bẹ̃. 8 Kiyesi i nisisiyi, emi li ọmọbinrin meji ti kò ti imọ̀ ọkunrin: emi bẹ̀ nyin, ẹ jẹ ki nmu wọn jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o si fi wọn ṣe bi o ti tọ́ loju nyin: ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi ṣa ni ki ẹ má ṣe ni nkan; nitorina ni nwọn sa ṣe wá si abẹ orule mi. 9 Nwọn si wipe, Bì sẹhin. Nwọn si tun wipe, Eyiyi wá iṣe atipo, on si fẹ iṣe onidajọ: njẹ iwọ li a o tilẹ ṣe ni buburu jù wọn lọ. Nwọn si rọlù ọkunrin na, ani Loti, nwọn si sunmọ ọ lati fọ́ ilẹkun. 10 Ṣugbọn awọn ọkunrin na nà ọwọ́ wọn, nwọn si fà Loti mọ́ ọdọ sinu ile, nwọn si tì ilẹkun. 11 Nwọn si bù ifọju lù awọn ọkunrin ti o wà li ẹnu-ọ̀na ile na, ati ewe ati àgba: bẹ̃ni nwọn dá ara wọn li agara lati ri ẹnu-ọ̀na.

Lọti Jáde kúrò ní Sodomu

12 Awọn ọkunrin na si wi fun Loti pe, Iwọ ni ẹnikan nihin pẹlu? ana rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ati ohunkohun ti iwọ ni ni ilu, mu wọn jade kuro nihinyi: 13 Nitori awa o run ibi yi, nitori ti igbe wọn ndi pupọ̀ niwaju OLUWA; OLUWA si rán wa lati run u. 14 Loti si jade, o si sọ fun awọn ana rẹ̀ ọkunrin, ti nwọn gbe awọn ọmọbinrin rẹ̀ ni iyawo, o wipe, Ẹ dide, ẹ jade kuro nihinyi; nitoriti OLUWA yio run ilu yi. Ṣugbọn o dabi ẹlẹtàn loju awọn ana rẹ̀. 15 Nigbati ọ̀yẹ si nla, nigbana li awọn angeli na le Loti ni ire wipe, Dide, mu aya rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji ti o wà nihin; ki iwọ ki o má ba run ninu ìya ẹ̀ṣẹ ilu yi. 16 Nigbati o si nlọra, awọn ọkunrin na nawọ mu u li ọwọ́, ati ọwọ́ aya rẹ̀, ati ọwọ́ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji; OLUWA sa ṣãnu fun u: nwọn si mu u jade, nwọn si fi i sẹhin odi ilu na. 17 O si ṣe nigbati nwọn mu wọn jade sẹhin odi tan, li o wipe, Sá asalà fun ẹmi rẹ; máṣe wò ẹhin rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe duro ni gbogbo pẹtẹlẹ; sá asalà lọ si ori oke, ki iwọ ki o má ba ṣegbe. 18 Loti si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi: 19 Kiyesi i na, ọmọ-ọdọ rẹ ti ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, iwọ si ti gbe ãnu rẹ ga, ti iwọ ti fi hàn mi ni gbigbà ẹmi mi là; ṣugbọn emi ki yio le salọ si ori oke, ki ibi ki o má ba bá mi nibẹ̀, ki emi ki o má ba kú. 20 Kiyesi i na, ilu yi sunmọ tosi lati sá si, kekere si ni: jọ̃, jẹ ki nsalà si ibẹ, (kekere ha kọ?) ọkàn mi yio si yè. 21 O si wi fun u pe, Wò o, mo gbà fun ọ niti ohun kan yi pẹlu pe, emi ki yio run ilu yi, nitori eyiti iwọ ti sọ. 22 Yara, salà sibẹ̀; nitori emi kò le ṣe ohun kan titi iwọ o fi de ibẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Soari.

Ìparun Sodomu ati Gomora

23 Orùn là sori ilẹ nigbati Loti wọ̀ ilu Soari. 24 Nigbana li OLUWA rọ̀jo sulfuri (okuta ina) ati iná lati ọdọ OLUWA lati ọrun wá si ori Sodomu on Gomorra: 25 O si run ilu wọnni, ati gbogbo Pẹtẹlẹ, ati gbogbo awọn ara ilu wọnni, ati ohun ti o hù jade ni ilẹ. 26 Ṣugbọn aya rẹ̀ bojuwò ẹhin lẹhin rẹ̀, o si di ọwọ̀n iyọ̀. 27 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o lọ si ibi ti o gbé duro niwaju OLUWA: 28 O si wò ìha Sodomu on Gomorra, ati ìha gbogbo ilẹ àgbegbe wọnni, o si wò o, si kiyesi i, ẽfin ilẹ na rú soke bi ẽfin ileru. 29 O si ṣe nigbati Ọlọrun run ilu àgbegbe wọnni ni Ọlọrun ranti Abrahamu, o si rán Loti jade kuro lãrin iparun na, nigbati o run ilu wọnni ninu eyiti Loti gbé ti joko.

Ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àwọn Ará Moabu ati Àwọn Ará Amoni

30 Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nitoriti o bẹ̀ru ati gbé Soari: o si ngbé inu ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji. 31 Eyi akọbi si wi fun atẹle pe, Baba wa gbó, kò si sí ọkunrin kan li aiye mọ́ ti yio wọle tọ̀ wa wá gẹgẹ bi iṣe gbogbo aiye. 32 Wá, jẹ ki a mu baba wa mu ọti-waini, awa o si sùn tì i, ki a le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa. 33 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na: eyi akọbi wọle tọ̀ ọ, o si sùn tì baba rẹ̀; on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. 34 O si ṣe, ni ijọ́ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sùn tì baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sùn tì i, ki awa ki o le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa. 35 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na pẹlu: aburo si dide, o si sùn tì i, on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. 36 Bẹ̃li awọn ọmọbinrin Loti mejeji loyun fun baba wọn. 37 Eyi akọ́bi si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Moabu: on ni baba awọn ara Moabu titi di oni. 38 Eyi atẹle, on pẹlu si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Ben-ammi: on ni baba awọn ọmọ Ammoni, titi di oni.

Genesisi 20

Abrahamu ati Abimeleki

1 ABRAHAMU si ṣí lati ibẹ̀ lọ si ilẹ ìha gusù, o si joko li agbedemeji Kadeṣi on Ṣuri; o si ṣe atipo ni Gerari. 2 Abrahamu si wi niti Sara aya rẹ̀ pe, Arabinrin mi ni: Abimeleki ọba Gerari si ranṣẹ, o si mu Sara. 3 Ṣugbọn Ọlọrun tọ̀ Abimeleki wá li ojuran li oru, o si wi fun u pe, kiyesi i, okú ni iwọ, nitori obinrin ti iwọ mu nì; nitori aya ọkunrin kan ni iṣe. 4 Ṣugbọn Abimeleki kò sunmọ ọ: o si wipe, OLUWA, iwọ o run orilẹ-ède olododo pẹlu? 5 On kọ ló ha wi fun mi pe arabinrin mi ni iṣe? on, obinrin tikalarẹ̀ si wipe, arakunrin mi ni: li otitọ inu ati alaiṣẹ̀ ọwọ́ mi, ni mo fi ṣe eyi. 6 Ọlọrun si wi fun u li ojuran pe, Bẹ̃ni, emi mọ̀ pe li otitọ inu rẹ ni iwọ ṣe eyi; nitorina li emi si ṣe dá ọ duro ki o má ba ṣẹ̀ mi: nitorina li emi kò ṣe jẹ ki iwọ ki o fọwọkàn a. 7 Njẹ nitori na mu aya ọkunrin na pada fun u; woli li on sa iṣe, on o si gbadura fun ọ, iwọ o si yè: bi iwọ kò ba si mu u pada, ki iwọ ki o mọ̀ pe, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo ẹniti o jẹ tirẹ. 8 Nitorina Abimeleki dide ni kutukutu owurọ̀, o si pè gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si wi gbogbo nkan wọnyi li eti wọn: ẹ̀ru si bà awọn enia na gidigidi. 9 Nigbana li Abimeleki pè Abrahamu, o si wi fun u pe, Kili o ṣe si wa yi? ẹ̀ṣẹ kini mo ṣẹ̀ ọ, ti iwọ fi mu ẹ̀ṣẹ nla wá si ori mi, ati si ori ijọba mi? iwọ hùwa si mi ti a ki ba hù. 10 Abimeleki si wi fun Abrahamu pe, Kini iwọ ri, ti iwọ fi ṣe nkan yi? 11 Abrahamu si wipe, Nitoriti mo rò pe, nitõtọ ẹ̀ru Ọlọrun kò sí nihinyi; nwọn o si pa mi nitori aya mi. 12 Ati pẹlupẹlu nitõtọ arabinrin mi ni iṣe, ọmọbinrin baba mi ni, ṣugbọn ki iṣe ọmọbinrin iya mi; o si di aya mi. 13 O si ṣe nigbati Ọlọrun mu mi rìn kiri lati ile baba mi wá, on ni mo wi fun u pe, eyi ni ore rẹ ti iwọ o ma ṣe fun mi; nibikibi ti awa o gbé de, ma wi nipa ti emi pe, arakunrin mi li on. 14 Abimeleki si mu agutan, ati akọmalu, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, o si fi wọn fun Abrahamu, o si mu Sara, aya rẹ̀, pada fun u. 15 Abimeleki si wipe, Kiyesi i, ilẹ mi niyi niwaju rẹ: joko nibiti o wù ọ. 16 O si wi fun Sara pe, Kiyesi i, mo fi ẹgbẹrun ìwọn fadaka fun arakunrin rẹ: kiyesi i, on ni ibojú fun ọ fun gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ, ati niwaju gbogbo awọn ẹlomiran li a da ọ lare. 17 Abrahamu si gbadura si Ọlọrun: Ọlọrun si mu Abimeleki li ara dá, ati aya rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin-ọdọ rẹ̀; nwọn si bimọ. 18 Nitori OLUWA ti sé inu awọn ara ile Abimeleki pinpin, nitori ti Sara, aya Abrahamu.

Genesisi 21

A Bí Isaaki

1 OLUWA si bẹ̀ Sara wò bi o ti wi, OLUWA si ṣe fun Sara bi o ti sọ. 2 Sara si loyun, o si bí ọmọkunrin kan fun Abrahamu li ogbologbo rẹ̀, li akokò igbati Ọlọrun dá fun u. 3 Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u. 4 Abrahamu si kọ Isaaki ọmọ rẹ̀ ni ilà, nigbati o di ọmọ ijọ́ mẹjọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. 5 Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u. 6 Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi. 7 O si wipe, Tani iba wi fun Abrahamu pe, Sara yio fi ọmú fun ọmọ mu? mo sá bí ọmọ kan fun u li ogbologbo rẹ̀. 8 Ọmọ na si dàgba, a si já a li ẹnu ọmú: Abrahamu si sè àse nla li ọjọ́ na ti a já Isaaki li ẹnu ọmú.

Wọ́n Lé Hagari ati Iṣimaeli Jáde nílé

9 Sara si ri ọmọ Hagari, ara Egipti, ti o bí fun Abrahamu, o nfi i rẹrin. 10 Nitorina li o ṣe wi fun Abrahamu pe, Lé ẹrubirin yi jade ti on ti ọmọ rẹ̀: nitoriti ọmọ ẹrubirin yi ki yio ṣe arole pẹlu Isaaki, ọmọ mi. 11 Ọrọ yi si buru gidigidi li oju Abrahamu nitori ọmọ rẹ̀. 12 Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ. 13 Ati ọmọ ẹrubirin na pẹlu li emi o sọ di orilẹ-ède, nitori irú-ọmọ rẹ ni iṣe. 14 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba. 15 Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan. 16 O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun. 17 Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà. 18 Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla. 19 Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu. 20 Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa. 21 O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá.

Majẹmu láàrin Abrahamu ati Abimeleki

22 O si ṣe li akokò na, ni Abimeleki ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, wi fun Abrahamu pe, Ọlọrun pẹlu rẹ ni gbogbo ohun ti iwọ nṣe. 23 Njẹ nisisiyi fi Ọlọrun bura fun mi nihinyi pe iwọ ki yio ṣe ẹ̀tan si mi, tabi si ọmọ mi, tabi si ọmọ-ọmọ mi: ṣugbọn gẹgẹ bi iṣeun ti mo ṣe si ọ, bẹ̃ni iwọ o si ṣe si mi, ati si ilẹ ti iwọ ti ṣe atipo ninu rẹ̀. 24 Abrahamu si wipe, emi o bura. 25 Abrahamu si ba Abimeleki wi nitori kanga omi kan, ti awọn ọmọ-ọdọ Abimeleki fi agbara gbà. 26 Abimeleki si wipe, emi kò mọ̀ ẹniti o ṣe nkan yi: bẹ̃ni iwọ kò sọ fun mi, bẹ̃li emi kò gbọ́, bikoṣe loni. 27 Abrahamu si mu agutan, ati akọmalu, o fi wọn fun Abimeleki; awọn mejeji si dá majẹmu. 28 Abrahamu si yà abo ọdọ-agutan meje ninu agbo si ọ̀tọ fun ara wọn. 29 Abimeleki si bi Abrahamu pe, kili a le mọ̀ abo ọdọ-agutan meje ti iwọ yà si ọ̀tọ fun ara wọn yi si? 30 O si wipe, nitori abo ọdọ-agutan meje yi ni iwọ o gbà lọwọ mi, ki nwọn ki o le ṣe ẹrí mi pe, emi li o wà kanga yi. 31 Nitorina li o ṣe pè ibẹ̀ na ni Beer-ṣeba; nitori nibẹ̀ li awọn mejeji gbé bura. 32 Bẹ̃ni nwọn si dá majẹmu ni Beer-ṣeba: nigbana li Abimeleki dide, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilẹ awọn ara Filistia. 33 Abrahamu si lọ́ igi tamariski kan ni Beer-ṣeba, nibẹ̀ li o si pè orukọ OLUWA, Ọlọrun Aiyeraiye. 34 Abrahamu si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọjọ́ pupọ̀.

Genesisi 22

Ọlọrun Pàṣẹ fún Abrahamu pé Kí Ó fi Isaaki Rúbọ

1 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi. 2 O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ. 3 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãrì, o si mu meji ninu awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati Isaaki, ọmọ rẹ̀, o si là igi fun ẹbọ sisun na, o si dide, o si lọ si ibi ti Ọlọrun sọ fun u. 4 Ni ijọ́ kẹta Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o ri ibẹ̀ na li okere. 5 Abrahamu si wi fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, pe, Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn ni, a o si gbadura, a o si tun pada tọ̀ nyin wá. 6 Abrahamu si mu igi ẹbọ sisun na, o si dì i rù Isaaki, ọmọ rẹ̀; o si mu iná li ọwọ́ rẹ̀, ati ọbẹ; awọn mejeji si jùmọ nlọ. 7 Isaaki si sọ fun Abrahamu baba rẹ̀, o si wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi, ọmọ mi. On si wipe, Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà? 8 Abrahamu si wipe, Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ̀ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun: bẹ̃li awọn mejeji jùmọ nlọ. 9 Nwọn si de ibi ti Ọlọrun ti wi fun u; Abrahamu si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si to igi rere, o si dì Isaaki ọmọ rẹ̀, o si dá a bulẹ li ori pẹpẹ lori igi na. 10 Abrahamu si nawọ rẹ̀, o si mu ọbẹ na lati dúmbu ọmọ rẹ̀. 11 Angeli OLUWA nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: o si dahùn pe, Emi niyi. 12 O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo. 13 Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀. 14 Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i. 15 Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji, 16 O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo: 17 Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn; 18 Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́. 19 Abrahamu si pada tọ̀ awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, nwọn si dide, nwọn si jùmọ lọ si Beer-ṣeba; Abrahamu si joko ni Beer-ṣeba. 20 O si ṣe, lẹhin nkan wọnyi, li a sọ fun Abrahamu pe, kiyesi i, Milka, on pẹlu si ti bimọ fun Nahori, arakunrin rẹ;

Àwọn Ìran Nahori

21 Husi akọ́bi rẹ̀, ati Busi arakunrin rẹ̀, ati Kemueli baba Aramu. 22 Ati Kesedi, ati Haso, ati Pildaṣi, ati Jidlafu, ati Betueli. 23 Betueli si bí Rebeka: awọn mẹjọ yi ni Milka bí fun Nahori, arakunrin Abrahamu. 24 Ati àle rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ Rehuma, on pẹlu si bí Teba, ati Gahamu, ati Tahaṣi, ati Maaka.

Genesisi 23

1 SARA si di ẹni ẹtadilãdoje ọdún: iye ọdún aiye Sara li eyi. 2 Sara si kú ni Kirjat-arba; eyi na ni Hebroni ni ilẹ Kenaani: Abrahamu si wá lati ṣọ̀fọ Sara ati lati sọkun rẹ̀. 3 Abrahamu si dide kuro niwaju okú rẹ̀, o si sọ fun awọn ọmọ Heti, wipe, 4 Alejò ati atipo li emi iṣe lọdọ nyin: ẹ fun mi ni ilẹ-isinku lãrin nyin, ki emi ki o le sin okú mi kuro ni iwaju mi. 5 Awọn ọmọ Heti si dá Abrahamu lohùn, nwọn si wi fun u pe, 6 Oluwa mi, gbọ́ ti wa: alagbara ọmọ-alade ni iwọ lãrin wa: ninu ãyò bojì wa ni ki o sin okú rẹ; kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio fi ibojì rẹ̀ dù ọ, ki iwọ ki o má sin okú rẹ. 7 Abrahamu si dide duro, o si tẹriba fun awọn enia ilẹ na, fun awọn ọmọ Heti. 8 O si ba wọn sọ̀rọ wipe, Bi o ba ṣe pe ti inu nyin ni ki emi ki o sin okú mi kuro ni iwaju mi, ẹ gbọ́ ti emi, ki ẹ si bẹ̀ Efroni, ọmọ Sohari, fun mi, 9 Ki o le fun mi ni ihò Makpela, ti o ni, ti o wà li opinlẹ oko rẹ̀; li oju-owo ni ki o fifun mi, fun ilẹ-isinku lãrin nyin. 10 Efroni si joko lãrin awọn ọmọ Heti: Efroni, ọmọ Heti, si dá Abrahamu lohùn li eti gbogbo awọn ọmọ Heti, ani li eti gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀ wipe, 11 Bẹ̃kọ, Oluwa mi, gbọ́ ti emi, mo fi oko na fun ọ, ati ihò ti o wà nibẹ̀, mo fi fun ọ: li oju awọn ọmọ awọn enia mi ni mo fi i fun ọ: sin okú rẹ. 12 Abrahamu si tẹriba niwaju awọn enia ilẹ na. 13 O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀. 14 Efroni si da Abrahamu li ohùn, o wi fun u pe, 15 Oluwa mi, gbọ́ ti emi: irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka ni ilẹ jẹ; kili eyini lãrin temi tirẹ? sa sin okú rẹ. 16 Abrahamu si gbọ́ ti Efroni; Abrahamu si wọ̀n iye fadaka na fun Efroni, ti o sọ li eti awọn ọmọ Heti, irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka, ti o kọja lọdọ awọn oniṣòwo. 17 Oko Efroni ti o wà ni Makpela, ti o wà niwaju Mamre, oko na, ati ihò ti o wà ninu rẹ̀, ati gbogbo igi ti o wà ni oko na, ti o wà ni gbogbo ẹba rẹ̀ yika, li a ṣe daju, 18 Fun Abrahamu ni ilẹ-ini, li oju awọn ọmọ Heti, li oju gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀. 19 Lẹhin eyi li Abrahamu sin Sara, aya rẹ̀, ninu ihò oko Makpela, niwaju Mamre: eyi nã ni Hebroni ni ilẹ Kenaani. 20 Ati oko na, ati ihò ti o wà nibẹ̀, li a ṣe daju fun Abrahamu, ni ilẹ isinku, lati ọwọ́ awọn ọmọ Heti wá.

Genesisi 24

Wọ́n Gbeyawo fún Isaaki

1 ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo. 2 Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi; 3 Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé: 4 Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi. 5 Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá? 6 Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. 7 OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá. 8 Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. 9 Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi. 10 Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori. 11 O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi. 12 O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi. 13 Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi: 14 Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi. 15 O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀. 16 Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke. 17 Iranṣẹ na si sure lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nmu omi diẹ ninu ladugbo rẹ. 18 O si dahùn pe, Mu, oluwa mi: o si yara, o sọ̀ ladugbo rẹ̀ ka ọwọ́, o si fun u mu. 19 Nigbati o si fun u mu tan, o si wipe, Emi o pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu, titi nwọn o fi mu tan. 20 O si yara, o si tú ladugbo rẹ̀ sinu ibumu, o si tun pada sure lọ si kanga lati pọn omi, o si pọn fun gbogbo awọn ibakasiẹ rẹ̀. 21 ọkunrin na si tẹjumọ ọ, o dakẹ, lati mọ̀ bi OLUWA mu ìrin on dara, bi bẹ̃kọ. 22 O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa; 23 O si bi i pe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi: àye wà ni ile baba rẹ fun wa lati wọ̀ si? 24 On si wi fun u pe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Milka, ti o bí fun Nahori, li emi iṣe. 25 O si wi fun u pe, Awa ni koriko ati sakasáka tó pẹlu, ati àye lati wọ̀ si. 26 Ọkunrin na si tẹriba, o si sìn OLUWA. 27 O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi. 28 Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀. 29 Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga. 30 O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na. 31 O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ. 32 Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀. 33 A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi. 34 O si wipe, Ọmọ-ọdọ Abrahamu li emi iṣe. 35 OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ. 36 Sara, aya oluwa mi, si bí ọmọ kan fun oluwa mi nigbati on (Sara) gbó tán: on li o si fi ohun gbogbo ti o ni fun. 37 Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé: 38 Bikoṣe ki iwọ ki o lọ si ile baba mi, ati si ọdọ awọn ibatan mi, ki o si fẹ́ aya fun ọmọ mi. 39 Emi si wi fun oluwa mi pe, Bọya obinrin na ki yio tẹle mi. 40 O si wi fun mi pe, OLUWA, niwaju ẹniti emi nrìn, yio rán angeli rẹ̀ pelu rẹ, yio si mu ọ̀na rẹ dara; iwọ o si fẹ́ aya fun ọmọ mi lati ọdọ awọn ibatan mi, ati lati inu ile baba mi: 41 Nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ninu ibura mi yi, nigbati iwọ ba de ọdọ awọn ibatan mi; bi nwọn kò ba si fi ẹnikan fun ọ, ọrùn rẹ yio si mọ́ kuro ninu ibura mi. 42 Emi si de si ibi kanga loni, mo si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, bi iwọ ba mu ọ̀na àjo mi ti mo nlọ nisisiyi dara: 43 Kiyesi i, mo duro li ẹba kanga omi; ki o si ṣẹ, pe nigbati wundia na ba jade wá ipọn omi, ti mo ba si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi li omi diẹ ki emi mu lati inu ladugbo rẹ; 44 Ti o si wi fun mi pe, Iwọ mu, emi o si pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu: ki on na ki o ṣe obinrin ti OLUWA ti yàn fun ọmọ oluwa mi. 45 Ki emi ki o si tó wi tán li ọkàn mi, kiyesi i, Rebeka jade de ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀; o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o pọn omi: emi si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi mu omi. 46 O si yara, o si sọ ladugbo rẹ̀ kalẹ kuro li ejika rẹ̀, o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu; bẹ̃li emi mu, o si fi fun awọn ibakasiẹ mu pẹlu. 47 Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀. 48 Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá. 49 Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi. 50 Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ. 51 Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi. 52 O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA. 53 Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀. 54 Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi. 55 Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ. 56 On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ. 57 Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀. 58 Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ. 59 Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ. 60 Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn. 61 Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ. 62 Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé. 63 Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá. 64 Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ. 65 Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀. 66 Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki. 67 Isaaki si mu u wá si inu agọ́ Sara, iya rẹ̀, o si mu Rebeka, o di aya rẹ̀; o si fẹ́ ẹ; a si tu Isaaki ninu lẹhin ikú iya rẹ̀.

Genesisi 25

Àwọn Ọmọ Mìíràn Tí Abrahamu Bí

1 ABRAHAMU si tun fẹ́ aya kan, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ketura. 2 O si bí Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaku, ati Ṣua fun u. 3 Jokṣani si bí Ṣeba, ati Dedani. Awọn ọmọ Dedani si ni Aṣurimu, ati Letuṣimu, ati Leumimu. 4 Ati awọn ọmọ Midiani; Efa, ati Eferi, ati Hanoku, ati Abida, ati Eldaa. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Ketura. 5 Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki. 6 Ṣugbọn awọn ọmọ àle ti Abrahamu ni, Abrahamu bùn wọn li ẹ̀bun, o si rán wọn lọ kuro lọdọ Isaaki, ọmọ rẹ̀, nigbati o wà lãye, si ìha ìla-õrùn, si ilẹ ìla-õrùn.

Ikú ati Ìsìnkú Abrahamu

7 Iwọnyi si li ọjọ́ ọdún aiye Abrahamu ti o wà, arun dí lọgọsan ọdún. 8 Abrahamu si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú li ogbologbo, arugbo, o kún fun ọjọ́; a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀. 9 Awọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣmaeli si sin i ni ihò Makpela, li oko Efroni, ọmọ Sohari enia Hitti, ti o wà niwaju Mamre; 10 Oko ti Abrahamu rà lọwọ awọn ọmọ Heti: nibẹ̀ li a gbé sin Abrahamu, ati Sara, aya rẹ̀. 11 O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.

Àwọn Ìran Iṣimaeli

12 Iwọnyi si ni iran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, ti Hagari, ara Egipti, ọmọbinrin ọdọ Sara bí fun Abrahamu: 13 Iwọnyi si li orukọ awọn ọmọkunrin Iṣmaeli, nipa orukọ wọn, ni iran idile wọn: akọ́bi Iṣmaeli, Nebajotu; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu, 14 Ati Miṣma, ati Duma, ati Masa; 15 Hadari, ati Tema, Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema: 16 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli, iwọnyi si li orukọ wọn, li ori-ori ilu wọn, li ori-ori ile odi wọn; ijoye mejila li orilẹ-ède wọn. 17 Iwọnyi si li ọdún aiye Iṣmaeli, ẹtadilogoje ọdún: o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú; a si kó o jọ pọ̀ pẹlu awọn enia rẹ. 18 Nwọn si tẹ̀dó lati Hafila lọ titi o fi de Ṣuri, ti o wà niwaju Egipti, bi iwọ ti nlọ sìha Assiria: o si kú niwaju awọn arakonrin rẹ̀ gbogbo.

Ìbí Esau ati Jakọbu

19 Iwọnyi si ni iran Isaaki, ọmọ Abrahamu: Abrahamu bí Isaaki: 20 Isaaki si jẹ ẹni ogoji ọdún, nigbati o mu Rebeka, ọmọbinrin Betueli, ara Siria ti Padan-aramu, arabinrin Labani ara Siria, li aya. 21 Isaaki si bẹ̀ OLUWA fun aya rẹ̀, nitoriti o yàgan: OLUWA si gbà ẹ̀bẹ rẹ̀, Rebeka, aya rẹ̀, si loyun. 22 Awọn ọmọ si njàgudu ninu rẹ̀: o si wipe, bi o ba ṣe pe bẹ̃ni yio ri, ẽṣe ti mo fi ri bayi? O si lọ bère lọdọ OLUWA. 23 OLUWA si wi fun u pe, orilẹ-ède meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le jù ekeji lọ; ẹgbọ́n ni yio si ma sìn aburo. 24 Nigbati ọjọ́ rẹ̀ ti yio bí si pé, si kiyesi i, ibeji li o wà ninu rẹ̀. 25 Akọ́bi si jade wá, o pupa, ara rẹ̀ gbogbo ri bí aṣọ onirun; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Esau. 26 Ati lẹhin eyini li arakunrin rẹ̀ jade wá, ọwọ́ rẹ̀ si dì gigĩsẹ Esau mu; a si sọ orukọ rẹ̀ ni Jakobu: Isaaki si jẹ ẹni ọgọta ọdún nigbati Rebeka bí wọn.

Esau Ta Ipò Àgbà Rẹ̀

27 Awọn ọmọdekunrin na si dàgba: Esau si ṣe ọlọgbọ́n ọdẹ, ara oko; Jakobu si ṣe ọbọrọ́ enia, a ma gbé inu agọ́. 28 Isaaki si fẹ́ Esau, nitori ti o njẹ ninu ẹran-ọdẹ rẹ̀: ṣugbọn Rebeka fẹ́ Jakobu. 29 Jakobu si pa ìpẹtẹ: Esau si ti inu igbẹ́ dé, o si rẹ̀ ẹ: 30 Esau si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ìpẹtẹ rẹ pupa nì bọ́ mi; nitori ti o rẹ̀ mi: nitori na li a ṣe npè orukọ rẹ̀ ni Edomu. 31 Jakobu si wipe, Tà ogún-ibí rẹ fun mi loni. 32 Esau si wipe, Sa wò o na, emi ni nkú lọ yi: ore kini ogún-ibí yi yio si ṣe fun mi? 33 Jakobu si wipe, Bura fun mi loni; o si bura fun u: o si tà ogún-ibí rẹ̀ fun Jakobu. 34 Nigbana ni Jakobu fi àkara ati ìpẹtẹ lentile fun Esau; o si jẹ, o si mu, o si dide, o si ba tirẹ̀ lọ: bayi ni Esau gàn ogún-ibí rẹ̀.

Genesisi 26

Isaaki Gbé ní Gerari

1 ÌYAN kan si mu ni ilẹ na, lẹhin ìyan ti o tetekọ mu li ọjọ́ Abrahamu. Isaaki si tọ̀ Abimeleki, ọba awọn ara Filistia lọ, si Gerari. 2 OLUWA si farahàn a, o si wipe, Máṣe sọkalẹ lọ si Egipti; joko ni ilẹ ti emi o wi fun ọ. 3 Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ. 4 Emi o si mu irú-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun, emi o si fi gbogbo ilẹ wọnyi fun irú-ọmọ rẹ; ati nipasẹ irú-ọmọ rẹ li a o bukún gbogbo orilẹ-ède aiye; 5 Nitoriti Abrahamu gbà ohùn mi gbọ́, o si pa ìlọ mi, aṣẹ mi, ìlana mi, ati ofin mi mọ́. 6 Isaaki si joko ni Gerari. 7 Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò. 8 O si ṣe nigbati o joko nibẹ̀ pẹ titi, ni Abimeleki, ọba awọn ara Filistia, wò ode li ojuferese, o si ri, si kiyesi i, Isaaki mba Rebeka aya rẹ̀ wẹ́. 9 Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀. 10 Abimeleki si wipe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? Bí ọkan ninu awọn enia bá lọ bá aya rẹ ṣe iṣekuṣe nkọ? iwọ iba si mu ẹ̀ṣẹ wá si ori wa. 11 Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú. 12 Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u: 13 Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi. 14 Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀. 15 Nitori gbogbo kanga ti awọn ọmọ-ọdọ baba rẹ̀ ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀, awọn ara Filistia dí wọn, nwọn si fi erupẹ dí wọn. 16 Abimeleki si wi fun Isaaki pe, Lọ kuro lọdọ wa; nitori ti iwọ lagbara pupọ̀ ju wa lọ. 17 Isaaki si ṣí kuro nibẹ̀, o si pa agọ́ rẹ̀ ni afonifoji Gerari, o si joko nibẹ̀. 18 Isaaki si tun wà kanga omi, ti nwọn ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀; nitori ti awọn ara Filistia ti dí wọn lẹhin ikú Abrahamu: o si pè orukọ wọn gẹgẹ bi orukọ ti baba rẹ̀ sọ wọn. 19 Awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wàlẹ li afonifoji nì, nwọn si kàn kanga isun omi nibẹ̀. 20 Awọn darandaran Gerari si mba awọn darandaran Isaaki jà, wipe, Ti wa li omi na: o si sọ orukọ kanga na ni Eseki; nitori ti nwọn bá a jà. 21 Nwọn si tun wà kanga miran, nwọn si tun jà nitori eyi na pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Sitna. 22 O si ṣí kuro nibẹ̀, o si wà kanga miran: nwọn kò si jà nitori rẹ̀: o si pè orukọ rẹ̀ ni Rehoboti; o si wipe, Njẹ nigbayi li OLUWA tó fi àye fun wa, awa o si ma bisi i ni ilẹ yi. 23 O si goke lati ibẹ̀ lọ si Beer-ṣeba. 24 OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi. 25 O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si kepè orukọ OLUWA, o si pa agọ́ rẹ̀ nibẹ̀: awọn ọmọ-ọdọ Isaaki si wà kanga kan nibẹ̀.

Abimeleki ati Isaaki Dá Majẹmu

26 Nigbana li Abimeleki tọ̀ ọ lati Gerari lọ, ati Ahusati, ọkan ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀. 27 Isaaki si bi wọn pe, Nitori kili ẹnyin ṣe tọ̀ mi wá, ẹnyin sa korira mi, ẹnyin si ti lé mi kuro lọdọ nyin? 28 Nwọn si wipe, Awa ri i nitõtọ pe, OLUWA wà pẹlu rẹ: awa si wipe, Njẹ nisisiyi jẹ ki ibura ki o wà lãrin wa, ani lãrin tawa tirẹ, ki awa ki o si ba iwọ dá majẹmu; 29 Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ. 30 O si sè àse fun wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu. 31 Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si bura fun ara wọn: Isaaki si rán wọn pada lọ, nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀ li alafia. 32 O si ṣe li ọjọ́ kanna li awọn ọmọ-ọdọ Isaaki wá, nwọn si rò fun u niti kanga ti nwọn wà, nwọn si wi fun u pe, Awa kàn omi. 33 O sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣeba: nitorina li orukọ ilu na ṣe njẹ Beer-ṣeba titi di oni.

Àwọn Obinrin Àjèjì Tí Esau Fẹ́

34 Esau si di ẹni ogoji ọdún nigbati o mu Juditi li aya, ọmọbinrin Beeri, ara Hitti, ati Baṣemati, ọmọbinrin Eloni, ara Hitti: 35 Ohun ti o ṣe ibinujẹ fun Isaaki ati fun Rebeka.

Genesisi 27

Isaaki Súre fún Jakọbu

1 O si ṣe, ti Isaaki gbó, ti oju rẹ̀ si nṣe bàibai, tobẹ̃ ti kò le riran, o pè Esau, ọmọ rẹ̀ akọ́bi, o si wi fun u pe, Ọmọ mi: on si dá a li ohùn pe, Emi niyi. 2 O si wipe, Wò o na, emi di arugbo, emi kò si mọ̀ ọjọ́ ikú mi; 3 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun ọdẹ rẹ, apó rẹ, ati ọrun rẹ, ki o si jade lọ si igbẹ́ ki o si pa ẹran-igbẹ́ fun mi wá: 4 Ki o si sè ẹran adidùn fun mi, bi irú eyiti mo fẹ́, ki o si gbé e tọ̀ mi wá, ki emi ki o jẹ: ki ọkàn mi ki o súre fun ọ ki emi to kú. 5 Rebeka si gbọ́ nigbati Isaaki nwi fun Esau, ọmọ rẹ̀. Esau si lọ si igbẹ́ lọ iṣọdẹ, lati pa ẹran-igbẹ́ wá. 6 Rebeka si wi fun Jakobu ọmọ rẹ̀ pe, Wò o, mo gbọ́ baba rẹ wi fun Esau arakunrin rẹ pe, 7 Mu ẹran-igbẹ́ fun mi wá, ki o si sè ẹran adidùn fun mi, ki emi ki o jẹ, ki emi ki o sure fun ọ niwaju OLUWA ṣaju ikú mi. 8 Njẹ nisisiyi, ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi, gẹgẹ bi emi o ti paṣẹ fun ọ. 9 Lọ nisisiyi sinu agbo-ẹran, ki o si mu ọmọ ewurẹ meji daradara fun mi lati ibẹ̀ wá: emi o si sè wọn li ẹran adidùn fun baba rẹ, bi irú eyiti o fẹ́: 10 Iwọ o si gbé e tọ̀ baba rẹ lọ, ki o le jẹ, ki o le súre fun ọ, ki on to kú. 11 Jakobu si wi fun Rebeka iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, enia onirun ni Esau arakunrin mi, alara ọbọrọ́ si li emi: 12 Bọya baba mi yio fọwọbà mi, emi o si dabi ẹlẹ̀tan fun u; emi o si mu egún wá si ori mi ki yio ṣe ibukún. 13 Iya rẹ̀ si wi fun u pe, lori mi ni ki egún rẹ wà, ọmọ mi: sá gbọ́ ohùn mi, ki o si lọ mu wọn fun mi wá. 14 O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́. 15 Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo: 16 O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀: 17 O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ. 18 O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi? 19 Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi. 20 Isaaki si wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Ẽti ri ti iwọ fi tete ri i bẹ̃, ọmọ mi? on si wipe, Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u tọ̀ mi wá ni. 21 Isaaki si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, sunmọ mi, ki emi ki o fọwọbà ọ, ọmọ mi, bi iwọ iṣe Esau, ọmọ mi nitotọ, bi bẹ̃kọ. 22 Jakobu si sunmọ Isaaki baba rẹ̀, o si fọwọbà a, o si wipe, Ohùn Jakobu li ohùn, ṣugbọn ọwọ́ li ọwọ́ Esau. 23 On kò si mọ̀ ọ, nitoriti ọwọ́ rẹ̀ ṣe onirun, bi ọwọ́ Esau, arakunrin rẹ̀: bẹ̃li o sure fun u. 24 O si wipe, Iwọ ni Esau ọmọ mi nitotọ? o si wipe, emi ni. 25 O si wipe, Gbé e sunmọ ọdọ mi, emi o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ mi, ki ọkàn mi ki o le sure fun ọ. O si gbé e sunmọ ọdọ rẹ̀, o si jẹ: o si gbé ọti-waini fun u, on si mu. 26 Isaaki baba rẹ̀ si wi fun u pe, Sunmọ ihín nisisiyi ọmọ mi, ki o si fi ẹnu kò mi li ẹnu. 27 O si sunmọ ọ, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: o si gbọ́ õrùn aṣọ rẹ̀, o si sure fun u, o si wipe, Wò o, õrùn ọmọ mi o dabi õrùn oko eyiti OLUWA ti busi. 28 Ọlọrun yio si fun ọ ninu ìri ọrun, ati ninu ọrá ilẹ, ati ọ̀pọlọpọ ọkà ati ọti-waini: 29 Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ. 30 O si ṣe, bi Isaaki ti pari ire isú fun Jakobu, ti Jakobu si fẹrẹ má jade tan kuro niwaju Isaaki baba rẹ̀, ni Esau, arakunrin rẹ̀ wọle de lati igbẹ́ ọdẹ rẹ̀ wá. 31 On pẹlu si ti sè ẹran adidùn, o si mu u tọ̀ baba rẹ̀ wá, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Ki baba mi ki o dide ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ rẹ̀, ki ọkàn rẹ le sure fun mi. 32 Isaaki baba rẹ̀ si bi i pe, Iwọ tani nì? on si wipe, Emi Esau, ọmọ rẹ akọbi ni. 33 Isaaki si warìri gidigidi rekọja, o si wipe, Tani nla? tali ẹniti o ti pa ẹran-igbẹ́, ti o si gbé e tọ̀ mi wá, emi si ti jẹ ninu gbogbo rẹ̀, ki iwọ ki o to de, emi si ti sure fun u? nitõtọ a o si bukún fun u. 34 Nigbati Esau gbọ́ ọ̀rọ baba rẹ̀, o fi igbe nlanla ta, o si sun ẹkun kikorò gidigidi, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Sure fun mi, ani fun emi pẹlu, baba mi. 35 O si wipe, Arakunrin rẹ fi erú wá, o si ti gbà ibukún rẹ lọ. 36 O si wipe, A kò ha pè orukọ rẹ̀ ni Jakobu ndan? nitori o jì mi li ẹsẹ̀ ni ìgba meji yi: o gbà ogún-ibi lọwọ mi; si kiyesi i, nisisiyi o si gbà ire mi lọ. O si wipe, Iwọ kò ha pa ire kan mọ́ fun mi? 37 Isaaki si dahùn o si wi fun Esau pe, Wõ, emi ti fi on ṣe oluwa rẹ, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li emi ti fi ṣe iranṣẹ rẹ̀; ati ọkà ati ọti-waini ni mo fi gbè e: ewo li emi o ha ṣe fun ọ nisisiyi, ọmọ mi? 38 Esau si wi fun baba rẹ̀ pe, Ire kanṣoṣo li o ni iwọ baba mi? sure fun mi, ani fun mi pẹlu, baba mi? Esau si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. 39 Isaaki baba rẹ̀ si dahùn o si wi fun u pe, Wõ, ibujoko rẹ yio jẹ ọrá ilẹ, ati ibi ìri ọrun lati oke wá; 40 Nipa idà rẹ ni iwọ o ma gbé, iwọ o si ma sìn arakunrin rẹ; yio si ṣe nigbati iwọ ba di alagbara tan, iwọ o já àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ. 41 Esau si korira Jakobu nitori ire ti baba rẹ̀ su fun u: Esau si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọjọ́ ọ̀fọ baba mi sunmọ-etile; nigbana li emi o pa Jakobu, arakunrin mi. 42 A si sọ ọ̀rọ Esau akọ́bi rẹ̀ wọnyi fun Rebeka: on si ranṣẹ o si pè Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo, o si wi fun u pe, Kiyesi i, Esau, arakunrin rẹ, ntù ara rẹ ninu niti rẹ lati pa ọ. 43 Njẹ nisisiyi ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi; si dide, sá tọ̀ Labani arakunrin mi lọ si Harani; 44 Ki o si bá a joko ni ijọ́ melo kan, titi ibinu arakunrin rẹ yio fi tuka; 45 Titi inu arakunrin rẹ yio fi tutu si ọ, ti yio si fi gbagbe ohun ti o fi ṣe e: nigbana li emi o ranṣẹ mu ọ lati ibẹ̀ wá: ẽṣe ti emi o fi fẹ́ ẹnyin mejeji kù ni ijọ́ kanṣoṣo?

Isaaki Rán Jakọbu Lọ sọ́dọ̀ Labani

46 Rebeka si wi fun Isaaki pe, Agara aiye mi ma dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakobu ba fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi irú awọn wọnyi yi iṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yi, aiye mi o ha ti ri?

Genesisi 28

1 ISAAKI si pè Jakobu, o si sùre fun u, o si kìlọ fun u, o si wi fun u pe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani. 2 Dide, lọ si Padan-aramu, si ile Betueli, baba iya rẹ; ki iwọ ki o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ wá ninu awọn ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ. 3 Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o si mu ọ bisi i, ki o si mu ọ rẹ̀ si i, ki iwọ ki o le di ọ̀pọlọpọ enia. 4 Ki o si fi ibukún Abrahamu fun ọ, fun iwọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ; ki iwọ ki o le ni ilẹ na ninu eyiti iwọ nṣe atipo, ti Ọlọrun fi fun Abrahamu. 5 Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau.

Esau Fẹ́ Aya Mìíràn

6 Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; 7 Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu: 8 Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀; 9 Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.

Àlá Jakọbu ní Bẹtẹli

10 Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani. 11 O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na. 12 O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀. 13 Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ. 14 Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye. 15 Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan. 16 Jakobu si jí li oju-orun rẹ̀, o si wipe, OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ̀. 17 Ẹrù si bà a, o si wipe, Ihinyi ti li ẹ̀ru tó! eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun. 18 Jakobu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si mu okuta ti o fi ṣe irọri rẹ̀, o si fi lelẹ fun ọwọ̀n, o si ta oróro si ori rẹ̀. 19 O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri. 20 Jakobu si jẹ́ ẹjẹ́ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ́ li ọ̀na yi ti emi ntọ̀, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora, 21 Ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi. 22 Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.

Genesisi 29

Jakọbu Dé sí Ilé Labani

1 JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn. 2 O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na. 3 Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀. 4 Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá. 5 O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ. 6 O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran. 7 O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn. 8 Nwọn si wipe, Awa kò le ṣe e, titi gbogbo awọn agbo-ẹran yio fi wọjọ pọ̀, ti nwọn o si fi yí okuta kuro li ẹnu kanga; nigbana li a le fun awọn agutan li omi. 9 Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn. 10 O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀. 11 Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. 12 Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀. 13 O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani. 14 Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan.

Jakọbu Sin Labani nítorí Rakẹli ati Lea

15 Labani si wi fun Jakobu pe, Iwọ o ha ma sìn mi li asan bi, nitoriti iwọ iṣe arakunrin mi? elo li owo iṣẹ rẹ, wi fun mi? 16 Labani si ni ọmọbinrin meji: orukọ ẹgbọ́n a ma jẹ Lea, orukọ aburo a si ma jẹ Rakeli. 17 Oju Lea kò li ẹwà, ṣugbọn Rakeli ṣe arẹwà, o si wù ni. 18 Jakobu si fẹ́ Rakeli; o si wipe, Emi o sìn ọ li ọdún meje nitori Rakeli, ọmọbinrin rẹ abikẹhin. 19 Labani si wipe, O san lati fi i fun ọ, jù ki nfi i fun ẹlomiran lọ: ba mi joko. 20 Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ. 21 Jakobu si wi fun Labani pe, Fi aya mi fun mi, nitoriti ọjọ́ mi pé, ki emi ki o le wọle tọ̀ ọ. 22 Labani si pè gbogbo awọn enia ibẹ̀ jọ, o si se àse. 23 O si ṣe li alẹ, o mú Lea ọmọbinrin rẹ̀, o sìn i tọ̀ ọ wá; on si wọle tọ̀ ọ lọ. 24 Labani si fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fun Lea, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. 25 O si ṣe, li owurọ, wò o, o jẹ́ Lea: o si wi fun Labani pe, Ẽwo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? nitori Rakeli ki mo ṣe sìn ọ, njẹ ẽhatiṣe ti o fi ṣe erú si mi? 26 Labani si wi fun u pe, A kò gbọdọ ṣe bẹ̃ ni ilẹ wa, lati sìn aburo ṣaju ẹgbọ́n. 27 Ṣe ọ̀sẹ ti eleyi pé, awa o si fi eyi fun ọ pẹlu, nitori ìsin ti iwọ o sìn mi li ọdún meje miran si i. 28 Jakobu si ṣe bẹ̃, o si ṣe ọ̀sẹ rẹ̀ pé: o si fi Rakeli ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya pẹlu. 29 Labani si fi Bilha, ọmọbinrin ọdọ rẹ̀, fun Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. 30 O si wọle tọ̀ Rakeli pẹlu, o si fẹ́ Rakeli jù Lea lọ, o si sìn i li ọdún meje miran si i.

Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Bí fún Jakọbu

31 Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan. 32 Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi. 33 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni. 34 O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi. 35 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.

Genesisi 30

1 NIGBATI Rakeli ri pe on kò bimọ fun Jakobu, Rakeli ṣe ilara arabinrin rẹ̀; o si wi fun Jakobu pe, Fun mi li ọmọ, bikoṣe bẹ̃ emi o kú. 2 Jakobu si binu si Rakeli: o si wipe, Emi ha wà ni ipò Ọlọrun, ẹniti o dù ọ li ọmọ bíbi? 3 On si wipe, Wò Bilha iranṣẹbinrin mi, wọle tọ̀ ọ; on ni yio si bí lori ẽkun mi, ki a le gbé mi ró pẹlu nipasẹ rẹ̀. 4 O si fi Bilha, iranṣẹbinrin rẹ̀, fun u li aya: Jakobu si wọle tọ̀ ọ. 5 Bilha si yún, o si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu. 6 Rakeli si wipe, Ọlọrun ti ṣe idajọ mi, o si ti gbọ́ ohùn mi, o si fi ọmọkunrin kan fun mi pẹlu: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Dani. 7 Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli, si tun yún, o si bi ọmọkunrin keji fun Jakobu. 8 Rakeli si wipe, Ijakadi nla ni mo fi bá arabinrin mi ja, emi si dá a: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Naftali. 9 Nigbati Lea ri pe on dẹkun ọmọ bíbi, o si mú Silpa, iranṣẹbinrin rẹ̀, o si fi i fun Jakobu li aya. 10 Silpa, iranṣẹbinrin Lea, si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu. 11 Lea si wipe, Ire de: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gadi. 12 Silpa iranṣẹbinrin Lea si bí ọmọkunrin keji fun Jakobu. 13 Lea si wipe, Alabukún fun li emi, nitori ti awọn ọmọbinrin yio ma pè mi li alabukún fun: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Aṣeri. 14 Li akokò ìgba ikore alikama, Reubeni si lọ, o si ri eso mandraki ni igbẹ́, o si mú wọn fun Lea iya rẹ̀ wá ile. Nigbana ni Rakeli wi fun Lea pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi ninu mandraki ọmọ rẹ. 15 O si wi fun u pe, Iṣe nkan kekere ti iwọ gbà ọkọ lọwọ mi? iwọ si nfẹ́ gbà mandraki ọmọ mi pẹlu? Rakeli si wipe, Nitori na ni yio ṣe sùn tì ọ li alẹ yi nitori mandraki ọmọ rẹ. 16 Jakobu si ti inu oko dé li aṣalẹ, Lea si jade lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Iwọ kò le ṣe aima wọle tọ̀ mi wá, nitori ti emi ti fi mandraki ọmọ mi bẹ̀ ọ li ọ̀wẹ. On si sùn tì i li oru na. 17 Ọlọrun si gbọ́ ti Lea, o si yún, o si bí ọmọkunrin karun fun Jakobu. 18 Lea si wipe, Ọlọrun san ọ̀ya mi fun mi, nitori ti mo fi iranṣẹbinrin mi fun ọkọ mi; o si pè orukọ rẹ̀ ni Issakari. 19 Lea si tun yún, o si bí ọmọkunrin kẹfa fun Jakobu. 20 Lea si wipe, Ọlọrun ti fun mi li ẹ̀bun rere; nigbayi li ọkọ mi yio tó ma bá mi gbé, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹfa fun u: o si pè orukọ rẹ̀ ni Sebuluni. 21 Nikẹhin rẹ̀ li o si bí ọmọbinrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Dina. 22 Ọlọrun si ranti Rakeli, Ọlọrun si gbọ́ tirẹ̀, o si ṣí i ni inu. 23 O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Ọlọrun mú ẹ̀gan mi kuro: 24 O si pè orukọ rẹ̀ ni Josefu; o si wipe, Ki OLUWA ki o fi ọmọkunrin kan kún u fun mi pẹlu.

Jakọbu Dúnàá Dúrà pẹlu Labani

25 O si ṣe, nigbati Rakeli bí Josefu tán, Jakobu si wi fun Labani pe, Rán mi jade lọ, ki emi ki o le ma lọ si ibiti mo ti wá, ati si ilẹ mi. 26 Fun mi li awọn obinrin mi, ati awọn ọmọ mi, nitori awọn ẹniti mo ti nsìn ọ, ki o si jẹ ki nma lọ: iwọ sá mọ̀ ìsin ti mo sìn ọ. 27 Labani si wipe, Duro, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, joko: nitori ti mo ri i pe, OLUWA ti bukún fun mi nitori rẹ. 28 O si wi fun u pe, Sọ iye owo iṣẹ rẹ, emi o si fi fun ọ. 29 O si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ bi emi ti sìn ọ, ati bi ẹran-ọ̀sin rẹ ti wà lọdọ mi. 30 Diẹ ni iwọ sá ti ní ki nto dé ọdọ rẹ, OLUWA si busi i li ọ̀pọlọpọ fun ọ lati ìgba ti mo ti dé: njẹ nisisiyi nigbawo li emi o pèse fun ile mi? 31 O si bi i pe, Kili emi o fi fun ọ? Jakobu si wi pe, Iwọ máṣe fun mi li ohun kan: bi iwọ o ba le ṣe eyi fun mi, emi o ma bọ́, emi o si ma ṣọ́ agbo-ẹran rẹ. 32 Emi o là gbogbo agbo-ẹran rẹ já loni, emi o mú gbogbo ẹran abilà ati alamì kuro nibẹ̀, ati gbogbo ẹran pupa rúsurusu kuro ninu awọn agutan, ati gbogbo ẹran alamì ati abilà ninu awọn ewurẹ: eyi ni yio si ma ṣe ọ̀ya mi. 33 Ododo mi yio si jẹ mi li ẹrí li ẹhin-ọla nigbati iwọ o wá wò ọ̀ya mi: gbogbo eyiti kò ba ṣe abilà ati alami ninu awọn ewurẹ, ti kò si ṣe pupa rúsurusu ninu awọn agutan, on na ni ki a kà si mi li ọrùn bi olè. 34 Labani si wipe, Wò o, jẹ ki o ri bi ọ̀rọ rẹ. 35 Li ọjọ́ na li o si yà awọn obukọ oni-tototó ati alamì, ati gbogbo awọn ewurẹ ti o ṣe abilà ati alamì, ati gbogbo awọn ti o ní funfun diẹ lara, ati gbogbo oni-pupa rúsurusu ninu awọn agutan, o si fi wọn lé awọn ọmọ rẹ̀ lọwọ. 36 O si fi ìrin ọjọ́ mẹta si agbedemeji on tikalarẹ̀ ati Jakobu: Jakobu si mbọ́ agbo-ẹran Labani iyokù. 37 Jakobu si mú ọpá igi-poplari tutù, ati igi haseli, ati kesnuti; o si bó wọn li abófin, o si mu ki funfun ti o wà lara awọn ọpá na hàn. 38 O si fi ọpá ti o bó lelẹ niwaju awọn agbo-ẹran li oju àgbará, ni ibi ọkọ̀ imumi, nigbati awọn agbo-ẹran wá mu omi, ki nwọn ki o le yún nigbati nwọn ba wá mumi. 39 Awọn agbo-ẹran si yún niwaju ọpá wọnni, nwọn si bí ẹran oni-tototó, ati abilà, ati alamì. 40 Jakobu si yà awọn ọdọ-agutan, o si kọju awọn agbo-ẹran si oni-tototó, ati gbogbo onìpupa rúsurusu ninu agbo-ẹran Labani: o si fi awọn agbo-ẹran si ọ̀tọ fun ara rẹ̀, kò si fi wọn sinu ẹran Labani. 41 O si ṣe, nigbati ẹran ti o lera jù ba yún, Jakobu a si fi ọpá na lelẹ niwaju awọn ẹran na li oju àgbará, ki nwọn o le ma yún lãrin ọpá wọnni. 42 Ṣugbọn nigbati awọn ẹran ba ṣe alailera, on ki ifi si i; bẹ̃li ailera ṣe ti Labani, awọn ti o lera jẹ́ ti Jakobu. 43 ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si li ẹran-ọ̀sin pupọ̀, ati iranṣẹbinrin, ati iranṣẹkunrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.

Genesisi 31

Jakọbu Sá kúrò lọ́dọ̀ Labani

1 O SI gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ Labani ti nwọn wipe, Jakobu kó nkan gbogbo ti iṣe ti baba wa; ati ninu ohun ti iṣe ti baba wa li o ti ní gbogbo ọrọ̀ yi. 2 Jakobu si wò oju Labani, si kiyesi i, kò ri si i bi ìgba atijọ. 3 OLUWA si wi fun Jakobu pe, Pada lọ si ilẹ awọn baba rẹ, ati si ọdọ awọn ara rẹ; emi o si pẹlu rẹ. 4 Jakobu si ranṣẹ o si pè Rakeli on Lea si pápa si ibi agbo-ẹran rẹ̀, 5 O si wi fun wọn pe, Emi wò oju baba nyin pe, kò ri si mi bi ìgba atijọ; ṣugbọn Ọlọrun baba mi ti wà pẹlu mi. 6 Ẹnyin si mọ̀ pe gbogbo agbara mi li emi fi sìn baba nyin. 7 Baba nyin si ti tàn mi jẹ, o si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa: ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ ki o pa mi lara. 8 Bi o ba si wi bayi pe, Awọn abilà ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí abilà: bi o ba si wi bayi, Awọn oni-tototó ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí oni-tototó. 9 Bẹ̃li Ọlọrun si gbà ẹran baba nyin, o si fi wọn fun mi. 10 O si ṣe li akokò ti awọn ẹran yún, mo si gbé oju mi soke, mo si ri li oju-alá, si kiyesi i, awọn obukọ ti o ngùn awọn ẹran jẹ́ oni-tototó, abilà, ati alamì. 11 Angeli Ọlọrun si sọ fun mi li oju-alá pe, Jakobu: emi si wipe, Emi niyi. 12 O si wipe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò, gbogbo awọn obukọ ti ngùn awọn ẹran li o ṣe tototó, abilà, ati alamì: nitori ti emi ti ri ohun gbogbo ti Labani nṣe si ọ. 13 Emi li Ọlọrun Beteli, nibiti iwọ gbé ta oróro si ọwọ̀n, nibiti iwọ gbè jẹ́ ẹjẹ́ fun mi: dide nisisiyi, jade kuro ni ilẹ yi, ki o si pada lọ si ilẹ ti a bi ọ. 14 Rakeli ati Lea si dahùn nwọn si wi fun u pe, Ipín, tabi ogún kan ha tun kù fun wa mọ́ ni ile baba wa? 15 Alejò ki on nkà wa si? nitori ti o ti tà wa; o si ti mù owo wa jẹ gúdu-gudu. 16 Nitori ọrọ̀ gbogbo ti Ọlọrun ti gbà lọwọ baba wa, eyinì ni ti wa, ati ti awọn ọmọ wa: njẹ nisisiyi ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun ọ, on ni ki o ṣe. 17 Nigbana ni Jakobu dide, o si gbé awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn aya rẹ̀ gùn ibakasiẹ. 18 O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani. 19 Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ. 20 Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ. 21 Bẹ̃li o kó ohun gbogbo ti o ní salọ: o si dide, o si kọja odò, o si kọju rẹ̀ si oke Gileadi.

Labani Lépa Jakọbu

22 A si wi fun Labani ni ijọ́ kẹta pe, Jakobu salọ. 23 O si mú awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si lepa rẹ̀ ni ìrin ijọ́ meje: o si bá a li oke Gileadi. 24 Ọlọrun si tọ̀ Labani, ara Siria wá li oru li oju-alá, o si wi fun u pe, Kiyesi ara rẹ, ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu. 25 Nigbana ni Labani bá Jakobu. Jakobu ti pa agọ́ rẹ̀ li oke na: ati Labani pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ dó li oke Gileadi. 26 Labani si wi fun Jakobu pe, Kini iwọ ṣe nì, ti iwọ tàn mi jẹ ti iwọ si kó awọn ọmọbinrin mi lọ bi ìgbẹsin ti a fi idà mú? 27 Ẽṣe ti iwọ fi salọ li aṣíri, ti iwọ si tàn mi jẹ; ti iwọ kò si wi fun mi ki emi ki o le fi ayọ̀ ati orin, ati ìlu, ati dùru, sìn ọ; 28 Ti iwọ kò si jẹ ki emi fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin mi li ẹnu? iwọ ṣiwere li eyiti iwọ ṣe yi. 29 O wà ni ipa mi lati ṣe nyin ni ibi: ṣugbọn Ọlọrun baba nyin ti sọ fun mi li oru aná pe, Kiyesi ara rẹ ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu. 30 Ati nisisiyi, iwọ kò le ṣe ailọ, nitori ti ọkàn rẹ fà gidigidi si ile baba rẹ, ṣugbọn ẽhaṣe ti iwọ fi jí awọn oriṣa mi lọ? 31 Jakobu si dahùn o si wi fun Labani pe, Nitori ti mo bẹ̀ru ni: nitori ti mo wipe, iwọ le fi agbara gbà awọn ọmọbinrin rẹ lọwọ mi. 32 Lọwọ ẹnikẹni ti iwọ ba ri awọn oriṣa rẹ ki o máṣe wà lãye: li oju awọn arakunrin wa wọnyi, wá ohun ti iṣe tirẹ lọdọ mi, ki o si mú u si ọdọ rẹ. Jakobu kò sa mọ̀ pe Rakeli ti jí wọn. 33 Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ. 34 Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn. 35 O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na. 36 Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃? 37 Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji. 38 Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ. 39 Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru. 40 Bayi ni mo wà; ongbẹ ngbẹ mi li ọsán, otutù si nmu mi li oru: orun mi si dá kuro li oju mi. 41 Bayi li o ri fun mi li ogún ọdún ni ile rẹ; mo sìn ọ li ọdún mẹrinla nitori awọn ọmọbinrin rẹ mejeji, ati li ọdún mẹfa nitori ohun-ọ̀sin rẹ: iwọ si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa. 42 Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná.

Labani ati Jakọbu Dá Majẹmu

43 Labani si dahùn o si wi fun Jakobu pe, Awọn ọmọbinrin wọnyi, awọn ọmọbinrin mi ni, ati awọn ọmọ wọnyi, awọn ọmọ mi ni, ati awọn ọwọ́-ẹran wọnyi ọwọ́-ẹran mi ni, ati ohun gbogbo ti o ri ti emi ni: kili emi iba si ṣe si awọn ọmọbinrin mi wọnyi loni, tabi si awọn ọmọ wọn ti nwọn bí? 44 Njẹ nisisiyi, wá, jẹ ki a bá ara wa dá majẹmu, temi tirẹ; ki o si ṣe ẹrí lãrin temi tirẹ. 45 Jakobu si mú okuta kan, o si gbé e ró ṣe ọwọ̀n. 46 Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na. 47 Labani si sọ orukọ rẹ̀ ni Jegari-Sahaduta: ṣugbọn Jakobu sọ ọ ni Galeedi. 48 Labani si wipe, Òkiti yi li ẹri lãrin temi tirẹ loni. Nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Galeedi: 49 Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa. 50 Bi iwọ ba pọ́n awọn ọmọbinrin mi li oju, tabi bi iwọ ba fẹ́ aya miran pẹlu awọn ọmọbinrin mi, kò sí ẹnikan pẹlu wa; wò o, Ọlọrun li ẹlẹri lãrin temi tirẹ. 51 Labani si wi fun Jakobu pe, Wò òkiti yi, si wò ọwọ̀n yi, ti mo gbé ró lãrin temi tirẹ. 52 Òkiti yi li ẹri, ọwọ̀n yi li ẹri, pe emi ki yio rekọja òkiti yi sọdọ rẹ; ati pe iwọ ki yio si rekọja òkiti yi ati ọwọ̀n yi sọdọ mi fun ibi. 53 Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Nahori, Ọlọrun baba wọn, ni ki o ṣe idajọ lãrin wa. Jakobu si fi ẹ̀ru Isaaki baba rẹ̀ bura. 54 Nigbana ni Jakobu rubọ lori oke na, o si pè awọn arakunrin rẹ̀ wá ijẹun: nwọn si jẹun, nwọn si fi gbogbo oru ijọ́ na sùn lori oke na. 55 Ni kutukutu owurọ̀ Labani si dide, o si fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ li ẹnu, o si sure fun wọn: Labani si dide, o si pada lọ si ipò rẹ̀.

Genesisi 32

Jakọbu Múra láti Pàdé Esau

1 JAKOBU si nlọ li ọ̀na rẹ̀, awọn angeli Ọlọrun si pade rẹ̀. 2 Nigbati Jakobu si ri wọn, o ni, Ogun Ọlọrun li eyi: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Mahanaimu. 3 Jakobu si ranṣẹ siwaju rẹ̀ si Esau, arakunrin rẹ̀, si ilẹ Seiri, pápa oko Edomu. 4 O si rán wọn wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau, oluwa mi; Bayi ni Jakobu iranṣẹ rẹ wi, Mo ti ṣe atipo lọdọ Labani, mo si ti ngbé ibẹ̀ titi o fi di isisiyi: 5 Mo si ní malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agbo-ẹran, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin: mo si ranṣẹ wá wi fun oluwa mi, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ. 6 Awọn onṣẹ si pada tọ̀ Jakobu wá, wipe, Awa dé ọdọ Esau, arakunrin rẹ, o si mbọ̀wá kò ọ, irinwo ọkunrin li o si wà pẹlu rẹ̀. 7 Nigbana li ẹ̀ru bà Jakobu gidigidi, ãjo si mú u, o si pín awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, ati awọn ọwọ́-ẹran, awọn ọwọ́-malu, ati awọn ibakasiẹ, si ipa meji; 8 O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là. 9 Jakobu si wipe, Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, OLUWA ti o wi fun mi pe, pada lọ si ilẹ rẹ, ati sọdọ awọn ara rẹ, emi o si ṣe ọ ni rere: 10 Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji. 11 Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ. 12 Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ. 13 O si sùn nibẹ̀ li alẹ ijọ́ na; o si mú ninu ohun ti o tẹ̀ ẹ li ọwọ li ọrẹ fun Esau, arakunrin rẹ̀; 14 Igba ewurẹ, on ogún obukọ, igba agutan, on ogún àgbo, 15 Ọgbọ̀n ibakasiẹ ti o ní wàra, pẹlu awọn ọmọ wọn, ogojì abo-malu on akọ-malu mẹwa, ogún abo-kẹtẹkẹtẹ, on ọmọ-kẹtẹkẹtẹ mẹwa. 16 O si fi wọn lé ọwọ́ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ni ọ̀wọ́ kọkan; o si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin ṣaju mi, ki ẹ si fi àlàfo si agbedemeji ọwọ́-ọwọ. 17 O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ? 18 Nigbana ni ki iwọ ki o wipe, Ti Jakobu iranṣẹ rẹ ni; ọrẹ ti o rán si Esau oluwa mi ni: si kiyesi i, on tikalarẹ̀ si mbẹ lẹhin wa. 19 Bẹ̃li o si fi aṣẹ fun ekeji, ati fun ẹkẹta, ati fun gbogbo awọn ti o tẹle ọwọ́ wọnni wipe, Bayibayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau nigbati ẹnyin ba ri i. 20 Ki ẹnyin ki o wi pẹlu pe, Kiyesi i, Jakobu iranṣẹ rẹ mbọ̀ lẹhin wa. Nitori ti o wipe, Emi o fi ọrẹ ti o ṣaju mi tù u loju, lẹhin eyini emi o ri oju rẹ̀, bọya yio tẹwọgbà mi. 21 Bẹ̃li ọrẹ na si kọja lọ niwaju rẹ̀: on tikalarẹ̀ si sùn li oru na ninu awọn ẹgbẹ.

Jakọbu jìjàkadì ní Penieli

22 O si dide li oru na, o si mú awọn aya rẹ̀ mejeji, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ mejeji, ati awọn ọmọ rẹ̀ mọkọkanla, o si kọja iwọdò Jabboku. 23 O si mú wọn, o si rán wọn si oke odò na, o si rán ohun ti o ní kọja si oke odò. 24 O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ. 25 Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi. 26 O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi. 27 O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu. 28 O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori. 29 Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀. 30 Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si. 31 Bi o si ti nkọja Penieli, õrùn là bá a, o si nmukun ni itan rẹ̀. 32 Nitori na li awọn ọmọ Israeli ki iṣe ijẹ iṣan ti ifà, ti o wà ni kòto itan, titi o fi di oni-oloni: nitori ti o fọwọkàn kòto egungun itan Jakobu ni iṣan ti ifà.

Genesisi 33

Jakọbu Pàdé Esau

1 JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji. 2 O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin. 3 On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀. 4 Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun. 5 O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni. 6 Nigbana li awọn iranṣẹbinrin sunmọ ọdọ rẹ̀, awọn ati awọn ọmọ wọn, nwọn si tẹriba. 7 Ati Lea pẹlu ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba: nikẹhin ni Josefu ati Rakeli si sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba. 8 O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni. 9 Esau si wipe, Emi ní tó, arakunrin mi; pa eyiti o ní mọ́ fun ara rẹ. 10 Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi; 11 Emi bẹ̀ ọ, gbà ẹ̀bun mi ti a mú fun ọ wá; nitori ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ ba mi ṣe, ati pe, nitori ti mo ní tó. O si rọ̀ ọ, on si gbà a. 12 O si wipe, Jẹ ki a bọ́ si ọ̀na ìrin wa, ki a si ma lọ, emi o si ṣaju rẹ. 13 Ṣugbọn on wi fun u pe, oluwa mi mọ̀ pe awọn ọmọ kò lera, ati awọn agbo-ẹran, ati ọwọ́-malu ati awọn ọmọ wọn wà pẹlu mi: bi enia ba si dà wọn li àdaju li ọjọ́ kan, gbogbo agbo ni yio kú. 14 Emi bẹ̀ ọ, ki oluwa mi ki o ma kọja nṣó niwaju iranṣẹ rẹ̀: emi o si ma fà wá pẹlẹ, gẹgẹ bi awọn ẹran ti o saju mi, ati bi ara awọn ọmọ ti le gbà, titi emi o fi dé ọdọ oluwa mi ni Seiri. 15 Esau si wipe, Njẹ ki emi ki o fi enia diẹ silẹ pẹlu rẹ ninu awọn enia ti o pẹlu mi. On si wipe, Nibo li eyini jasi, ki emi ki o sa ri õre-ọfẹ li oju oluwa mi. 16 Esau si pada li ọjọ́ na li ọ̀na rẹ̀ lọ si Seiri. 17 Jakobu si rìn lọ si Sukkotu, o si kọ́ ile fun ara rẹ̀, o si pa agọ́ fun awọn ẹran rẹ̀: nitorina li a ṣe sọ orukọ ibẹ̀ na ni Sukkotu. 18 Jakobu si wá li alafia, si ilu Ṣekemu ti o wà ni ilẹ Kenaani, nigbati o ti Padan-aramu dé: o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ilu na. 19 O si rà oko biri kan, nibiti o gbé ti pa agọ́ rẹ̀ lọwọ awọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, li ọgọrun owo fadaka. 20 O si tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ̀, o si sọ orukọ rẹ̀ ni El-Elohe-Israeli.

Genesisi 34

Wọ́n fi Ipá bá Dina Lòpọ̀

1 DINA ọmọbinrin Lea, ti o bí fun Jakobu si jade lọ lati wò awọn ọmọbinrin ilu na. 2 Nigbati Ṣekemu, ọmọ Hamori, ara Hiffi, ọmọ alade ilu na ri i, o mú u, o si wọle tọ̀ ọ, o si bà a jẹ́. 3 Ọkàn rẹ̀ si fà mọ́ Dina, ọmọbinrin Jakobu, o si fẹ́ omidan na, o si sọ̀rọ rere fun omidan na. 4 Ṣekemu si sọ fun Hamori baba rẹ̀ pe, Fẹ́ omidan yi fun mi li aya. 5 Jakobu si gbọ́ pe o ti bà Dina ọmọbinrin on jẹ́; njẹ awọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu awọn ẹran ni pápa: Jakobu si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ titi nwọn fi dé. 6 Hamori, baba Ṣekemu, si jade tọ̀ Jakobu lọ lati bá a sọ̀rọ. 7 Awọn ọmọ Jakobu si ti oko dé nigbati nwọn gbọ́: inu awọn ọkunrin na si bàjẹ́, inu si ru wọn gidigidi, nitori ti o ṣe ohun buburu ni Israeli, niti o bá ọmọbinrin Jakobu dàpọ: ohun ti a ki ba ti ṣe. 8 Hamori si bá wọn sọ̀rọ pe, Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, nfẹ́ ọmọbinrin nyin; emi bẹ̀ nyin, ẹ fi i fun u li aya. 9 Ki ẹnyin ki o si bá wa gbeyawo, ki ẹnyin ki o si fi awọn ọmọbinrin nyin fun wa, ki ẹnyin ki o si ma mú awọn ọmọbinrin wa. 10 Ẹnyin o si ma bá wa gbé: ilẹ yio si wà niwaju nyin, ẹnyin o joko ki ẹ si ma ṣòwo ninu rẹ̀, ki ẹ si ma ní iní ninu rẹ̀. 11 Ṣekemu si wi fun baba omidan na ati fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju nyin, ohun ti ẹnyin o si kà fun mi li emi o fi fun nyin. 12 Ẹ bère ana lọwọ mi ati ẹ̀bun bi o ti wù ki o pọ̀ to, emi o si fi fun nyin gẹgẹ bi ẹnyin o ti kà fun mi: ṣugbọn ẹ fun mi li omidan na li aya. 13 Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́: 14 Nwọn si wi fun wọn pe, Awa kò le ṣe nkan yi lati fi arabinrin wa fun ẹni alaikọlà, nitori ohun àbuku ni fun wa; 15 Kiki ninu eyi li awa le jẹ fun nyin: bi ẹnyin o ba wà bi awa, pe ki a kọ olukuluku ọkunrin nyin li ilà. 16 Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna. 17 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti wa lati kọlà; njẹ awa o mú ọmọbinrin wa, awa o si ba ti wa lọ. 18 Ọ̀rọ wọn si dún mọ́ Hamori, ati Ṣekemu, ọmọ Hamori. 19 Ọdọmọkunrin na kò si pẹ́ titi lati ṣe nkan na, nitoriti o fẹ́ ọmọbinrin Jakobu; o si li ọlá jù gbogbo ara ile baba rẹ̀ lọ. 20 Ati Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wá si ẹnubode ilu wọn, nwọn si bá awọn ara ilu wọn sọ̀rọ wipe, 21 Awọn ọkunrin wọnyi mbá wa gbé li alafia; nitorina ẹ jẹ ki nwọn ki o ma gbé ilẹ yi, ki nwọn ki o si ma ṣòwo nibẹ̀; kiyesi i, ilẹ sa gbàye tó niwaju wọn; ẹnyin jẹ ki a ma fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, ki awa ki o si ma fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn. 22 Kìki ninu eyi li awọn ọkunrin na o ṣe jẹ fun wa, lati ma bá wa gbé, lati di enia kan, bi gbogbo ọkunrin inu wa ba kọlà, gẹgẹ bi nwọn ti kọlà. 23 Tiwa kọ ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ati gbogbo ohunọ̀sin wọn yio ha ṣe? ki a sa jẹ fun wọn nwọn o si ma ba wa joko, 24 Gbogbo awọn ti njade li ẹnubode ilu wọn si fetisi ti Hamori ati ti Ṣekemu ọmọ rẹ̀; a si kọ gbogbo awọn ọkunrin ni ilà, gbogbo ẹniti o nti ẹnubode wọn jade. 25 O si ṣe ni ọjọ́ kẹta, ti ọgbẹ wọn kan, ni awọn ọmọkunrin Jakobu meji si dide, Simeoni ati Lefi, awọn arakunrin Dina, olukuluku nwọn mú idà rẹ̀, nwọn si fi igboyà wọ̀ ilu na, nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin. 26 Nwọn si fi oju idà pa Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀, nwọn si mú Dina jade kuro ni ile Ṣekemu, nwọn si jade lọ. 27 Awọn ọmọ Jakobu si wọle awọn ti a pa, nwọn si kó ilu na lọ, nitori ti nwọn bà arabinrin wọn jẹ́. 28 Nwọn kó agutan wọn, ati akọmalu wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ohun ti o wà ni ilu na, ati eyiti o wà li oko. 29 Ati ọrọ̀ wọn gbogbo, ati gbogbo ọmọ wọn wẹ́rẹ, ati aya wọn ni nwọn dì ni igbekun, nwọn si kó ohun gbogbo ti o wà ninu ile lọ. 30 Jakobu si wi fun Simeoni on Lefi pe, Ẹnyin mu wahalà bá mi niti ẹnyin mu mi di õrun ninu awọn onilẹ, ninu awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi: bi emi kò si ti pọ̀ ni iye, nwọn o kó ara wọn jọ si mi, nwọn o si pa mi: a o si pa mi run, emi ati ile mi. 31 Nwọn si wipe, Ki on ki o ha ṣe si arabinrin wa bi ẹnipe si panṣaga?

Genesisi 35

Ọlọrun Súre fún Jakọbu ní Bẹtẹli

1 ỌLỌRUN si wi fun Jakobu pe, Dide goke lọ si Beteli ki o si joko nibẹ̀, ki o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, fun Ọlọrun, ti o farahàn ọ, nigbati iwọ sá kuro niwaju Esau, arakunrin rẹ. 2 Nigbana ni Jakobu wi fun awọn ara ile rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ti o wà li ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mú àjeji oriṣa ti o wà lọwọ nyin kuro, ki ẹnyin ki o si sọ ara nyin di mimọ́, ki ẹnyin ki o si pa aṣọ nyin dà: 3 Ẹ si jẹ ki a dide, ki a si goke lọ si Beteli; nibẹ̀ li emi o si gbé tẹ́ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ti o da mi li ohùn li ọjọ́ ipọnju mi, ẹniti o si wà pẹlu mi li àjo ti mo rè. 4 Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu. 5 Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu. 6 Bẹ̃ni Jakobu si wá si Lusi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, eyinì ni Beteli, on ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀. 7 O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni El-bet-el: nitori pe nibẹ̀ li Ọlọrun tọ̀ ọ wá, nigbati o sá kuro niwaju arakunrin rẹ̀. 8 Ṣugbọn Debora olutọ́ Rebeka kú, a si sin i nisalẹ Beteli labẹ igi oaku kan: orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Alloni-bakutu. 9 Ọlọrun si tún farahàn Jakobu, nigbati o ti Padan-aramu bọ̀, o si sure fun u. 10 Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli. 11 Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá; 12 Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun. 13 Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ. 14 Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀. 15 Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.

Ikú Rakẹli

16 Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u. 17 O si ṣe nigbati o wà ninu irọbí, ni iyãgba wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu. 18 O si ṣe, bi ọkàn rẹ̀ ti nlọ̀ (o sa kú) o sọ orukọ rẹ̀ ni Ben-oni: ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ ni Benjamini. 19 Rakeli si kú, a si sin i li ọ̀na Efrati, ti iṣe Betlehemu. 20 Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ li oju-õri rẹ̀, eyinì ni Ọwọ̀n oju-õri Rakeli titi di oni-oloni. 21 Israeli si nrìn lọ, o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ile iṣọ Ederi.

Àwọn Ọmọ Jakọbu

22 O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila. 23 Awọn ọmọ Lea; Reubẹni, akọ́bi Jakobu, ati Simeoni, ati Lefi, ati Judah, ati Issakari, ati Sebuluni. 24 Awọn ọmọ Rakeli; Josefu, ati Benjamini: 25 Ati awọn ọmọ Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli; Dani, ati Naftali: 26 Ati awọn ọmọ Silpa, iranṣẹbinrin Lea; Gadi ati Aṣeri. Awọn wọnyi li ọmọ Jakobu, ti a bí fun u ni Padanaramu.

Ikú Isaaki

27 Jakobu si dé ọdọ Isaaki baba rẹ̀, ni Mamre, si Kiriat-arba, ti iṣe Hebroni, nibiti Abrahamu ati Isaaki gbé ṣe atipo pẹlu. 28 Ọjọ́ Isaaki si jẹ́ ọgọsan ọdún. 29 Isaaki si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, o gbó, o si kún fun ọjọ́, awọn ọmọ rẹ̀, Esau ati Jakobu si sin i.

Genesisi 36

Àwọn Ìran Esau

1 WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu. 2 Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi; 3 Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu. 4 Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli; 5 Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani. 6 Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀. 7 Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn. 8 Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu. 9 Wọnyi si ni iran Esau, baba awọn ara Edomu, li oke Seiri: 10 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau. 11 Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi. 12 Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau. 13 Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. 14 Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora. 15 Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori, 16 Kora olori, Gatamu olori, Amaleki olori: wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Elifasi wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Ada. 17 Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli ọmọ Esau; Nahati olori, Sera olori, Ṣamma olori, Misa olori; wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Reueli wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. 18 Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana. 19 Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn.

Àwọn Ìran Seiri

20 Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, 21 Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu. 22 Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna. 23 Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu. 24 Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀. 25 Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana. 26 Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani. 27 Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani. 28 Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani. 29 Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori, 30 Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.

Àwọn Ọba Edomu

31 Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli. 32 Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba. 33 Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀. 34 Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀. 35 Huṣamu si kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ẹniti o kọlù Midiani ni igbẹ́ Moabu si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Afiti. 36 Hadadi si kú, Samla ti Masreka si jọba ni ipò rẹ̀. 37 Samla si kú, Ṣaulu ti Rehobotu leti odò nì si jọba ni ipò rẹ̀. 38 Ṣaulu si kú, Baal-hanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀. 39 Baal-hanani ọmọ Akbori si kú, Hadari si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pau; Mehetabeli si li orukọ aya rẹ̀, ọmọbinrin Metredi, ọmọbinrin Mesahabu. 40 Wọnyi si li orukọ awọn olori ti o ti ọdọ Esau wá, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ipò wọn, nipa orukọ wọn; Timna olori, Alfa olori, Jeteti olori; 41 Aholibama olori, Ela olori, Pinoni olori; 42 Kenasi olori, Temani olori, Mibsari olori; 43 Magdieli olori, Iramu olori: wọnyi li awọn olori Edomu, nipa itẹ̀dó wọn ni ilẹ iní wọn: eyi ni Esau, baba awọn ara Edomu.

Genesisi 37

Josẹfu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

1 JAKOBU si joko ni ilẹ ti baba rẹ̀ ti ṣe atipo, ani ilẹ Kenaani. 2 Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn. 3 Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u. 4 Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia. 5 Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i. 6 O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá. 7 Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi. 8 Awọn arakunrin rẹ̀ si wi fun u pe, Iwọ o ha jọba lori wa bi? tabi iwọ o ṣe olori wa nitõtọ? nwọn si tun korira rẹ̀ si i nitori alá rẹ̀ ati nitori ọ̀rọ rẹ̀. 9 O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi. 10 O si rọ́ ọ fun baba rẹ̀, ati fun awọn arakunrin rẹ̀: baba rẹ̀ si bá a wi, o si wi fun u pe, Alá kili eyi ti iwọ lá yi? emi ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ yio ha wá nitõtọ, lati foribalẹ fun ọ bi? 11 Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.

Wọ́n Ta Josẹfu Lẹ́rú sí Ijipti

12 Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ lati bọ́ agbo-ẹran baba wọn ni Ṣekemu. 13 Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi. 14 O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu. 15 Ọkunrin kan si ri i, si wò o, o nrìn kakiri ni pápa: ọkunrin na si bi i pe, Kini iwọ nwá? 16 On si wipe, Emi nwá awọn arakunrin mi: mo bẹ̀ ọ, sọ ibi ti nwọn gbé mbọ́ agbo-ẹran wọn fun mi. 17 Ọkunrin na si wipe, Nwọn ti lọ kuro nihin; nitori mo gbọ́, nwọn nwipe, ẹ jẹ ki a lọ si Dotani. Josefu si lepa awọn arakunrin rẹ̀, o si ri wọn ni Dotani. 18 Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a. 19 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá. 20 Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri. 21 Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀. 22 Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ. 23 O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀; 24 Nwọn si mú u, nwọn si gbe e sọ sinu ihò kan: ihò na si gbẹ, kò li omi. 25 Nwọn si joko lati jẹun: nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn si wò, si kiyesi i, ọwọ́-èro ara Iṣmaeli nti Gileadi bọ̀; ti awọn ti ibakasiẹ ti o rù turari ati ikunra ati ojia, nwọn nmú wọn lọ si Egipti. 26 Judah si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ere ki li o jẹ́ bi awa ba pa arakunrin wa, ti a si bò ẹ̀jẹ rẹ̀? 27 Ẹ wá ẹ jẹ ki a tà a fun awọn ara Iṣmaeli ki a má si fọwọ wa kàn a; nitori arakunrin wa ati ara wa ni iṣe. Awọn arakunrin rẹ̀ si gbà tirẹ̀. 28 Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti. 29 Reubeni si pada lọ si ihò; si wò o, Josefu kò sí ninu ihò na; o si fà aṣọ rẹ̀ ya. 30 O si pada tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wipe, Ọmọde na kò sí; ati emi, nibo li emi o gbé wọ̀? 31 Nwọn si mú ẹ̀wu Josefu, nwọn si pa ọmọ ewurẹ kan, nwọn si rì ẹ̀wu na sinu ẹ̀jẹ na. 32 Nwọn si fi ẹ̀wu alarabara aṣọ na ranṣẹ, nwọn si mú u tọ̀ baba wọn wá; nwọn si wipe, Eyi li awa ri: mọ̀ nisisiyi bi ẹ̀wu ọmọ rẹ ni, bi on kọ́. 33 On si mọ̀ ọ, o si wipe, Ẹ̀wu ọmọ mi ni; ẹranko buburu ti pa a jẹ; li aiṣe aniani, a ti fà Josefu ya pẹrẹpẹrẹ. 34 Jakobu si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si ṣọ̀fọ ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ pupọ̀. 35 Ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ obinrin dide lati ṣìpẹ fun u; ṣugbọn o kọ̀ lati gbipẹ̀; o si wipe, Ninu ọ̀fọ li emi o sa sọkalẹ tọ̀ ọmọ mi lọ si isà-okú. Bayi ni baba rẹ̀ sọkun rẹ̀. 36 Awọn ara Midiani si tà a si Egipti fun Potifari, ijoye Farao kan, ati olori ẹṣọ́.

Genesisi 38

Juda ati Tamari

1 O SI ṣe li akokò na, ni Judah sọkalẹ lọ kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, o si yà sọdọ ara Adullamu kan, orukọ ẹniti ijẹ́ Hira. 2 Judah si ri ọmọbinrin ara Kenaani kan nibẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Ṣua; o si mú u, o si wọle tọ̀ ọ. 3 O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Eri. 4 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Onani. 5 O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣela: o wà ni Kesibu, nigbati o bí i. 6 Judah si fẹ́ aya fun Eri akọ́bi rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Tamari. 7 Eri akọ́bi Judah si ṣe enia buburu li oju OLUWA; OLUWA si pa a. 8 Judah si wi fun Onani pe, Wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ lọ, ki o si ṣú u li opó, ki o si bimọ si ipò arakunrin rẹ. 9 Onani si mọ̀ pe, irú-ọmọ ki yio ṣe tirẹ̀; o si ṣe bi o ti wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ̀ lọ, o si dà a silẹ, ki o má ba fi irú-ọmọ fun arakunrin rẹ̀. 10 Ohun ti o si ṣe buru loju OLUWA, nitori na li OLUWA pa a pẹlu. 11 Nigbana ni Judah wi fun Tamari aya ọmọ rẹ̀ pe, Joko li opó ni ile baba rẹ, titi Ṣela ọmọ mi o fi dàgba: nitori o wipe, Ki on má ba kú pẹlu, bi awọn arakunrin rẹ̀. Tamari si lọ, o si joko ni ile baba rẹ̀. 12 Nigbati ọjọ́ si npẹ́, ọmọbinrin Ṣua, aya Juda kú; Judah si gbipẹ̀, o si tọ̀ awọn olurẹrun agutan rẹ̀, lọ si Timnati, on ati Hira ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu. 13 A si wi fun Tamari pe, Kiyesi i, baba ọkọ rẹ lọ si Timnati lati rẹrun agutan rẹ̀. 14 O si bọ́ aṣọ opó rẹ̀ kuro li ara rẹ̀, o si fi iboju bò ara rẹ̀, o si roṣọ, o si joko li ẹnubode Enaimu, ti o wà li ọ̀na Timnati; nitoriti o ri pe Ṣela dàgba, a kò si fi on fun u li aya. 15 Nigbati Judah ri i, o fi i pè panṣaga; nitori o boju rẹ̀. 16 O si yà tọ̀ ọ li ẹba ọ̀na, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, wá na, jẹ ki emi ki o wọle tọ̀ ọ; (on kò sa mọ̀ pe aya ọmọ on ni iṣe.) On si wipe Kini iwọ o fi fun mi, ki iwọ ki o le wọle tọ̀ mi? 17 O si wipe, emi o rán ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. On si wipe, iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi rán a wá? 18 O si bi i pe, Ògo kili emi o fi fun ọ? on si wipe, Èdidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpá rẹ ti o wà li ọwọ́ rẹ; o si fi wọn fun u, o si wọle tọ̀ ọ lọ, on si ti ipa ọdọ rẹ̀ yún. 19 On si dide, o ba tirẹ̀ lọ, o si bọ́ iboju rẹ̀ lelẹ kuro lara rẹ̀, o si mú aṣọ opó rẹ̀ ró. 20 Judah si rán ọmọ ewurẹ na lati ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu na lọ, lati gbà ògo nì wá lọwọ obinrin na: ṣugbọn on kò ri i. 21 Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin. 22 O si pada tọ̀ Judah lọ, o si wipe, Emi kò ri i; ati pẹlu awọn ọkunrin ara ibẹ̀ na wipe, Kò sí panṣaga kan nibẹ̀. 23 Judah si wipe, Jẹ ki o ma mú u fun ara rẹ̀, ki oju ki o má tì wa: kiyesi i, emi rán ọmọ ewurẹ yi, iwọ kò si ri i. 24 O si ṣe niwọ̀n oṣù mẹta lẹhin rẹ̀, ni a wi fun Judah pe, Tamari aya ọmọ rẹ ṣe àgbere; si kiyesi i pẹlu, o fi àgbere loyun. Judah si wipe, Mú u jade wá, ki a si dána sun u. 25 Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá. 26 Judah si jẹwọ, o si wipe, O ṣe olododo jù mi lọ; nitori ti emi kò fi i fun Ṣela ọmọ mi. On kò si mọ̀ ọ mọ́ lai. 27 O si ṣe li akokò ti o nrọbí, si kiyesi i, ìbejì wà ni inu rẹ̀. 28 O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade. 29 O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi: 30 Nikẹhin li arakunrin rẹ̀ jade, ti o li okùn ododó li ọwọ́ rẹ̀: a si sọ orukọ rẹ̀ ni Sera.

Genesisi 39

Josẹfu ati Aya Pọtifari

1 A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀. 2 OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na. 3 Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀. 4 Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ. 5 O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko. 6 O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia. 7 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe. 8 Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ: 9 Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun? 10 O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe. 11 O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀. 12 On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode. 13 O si ṣe, nigbati o ri i pe Josefu jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, ti o si sá jade, 14 Nigbana li o kepè awọn ọkunrin ile rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ wò o, o mú Heberu kan wọle tọ̀ wa wá lati fi wa ṣe ẹlẹyà; o wọle tọ̀ mi wá lati bá mi ṣe, mo si kigbe li ohùn rara: 15 O si ṣe, nigbati o gbọ́ pe mo gbé ohùn mi soke ti mo si kigbe, o jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá, o bọ sode. 16 O si fi aṣọ Josefu lelẹ li ẹba ọdọ rẹ̀, titi oluwa rẹ̀ fi bọ̀wá ile. 17 O si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi pe, Ẹrú Heberu ti iwọ mu tọ̀ wa, o wọle tọ̀ mi lati fi mi ṣe ẹlẹyà: 18 O si ṣe, bi mo ti gbé ohùn mi soke ti mo si ké, o si jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá jade. 19 O si ṣe, nigbati oluwa rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ aya rẹ̀, ti o sọ fun u wipe, Bayibayi li ẹrú rẹ ṣe si mi; o binu gidigidi. 20 Oluwa Josefu si mú u, o si fi i sinu túbu, nibiti a gbé ndè awọn ara túbu ọba; o si wà nibẹ̀ ninu túbu. 21 Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu. 22 Onitúbu si fi gbogbo awọn ara túbu ti o wà ninu túbu lé Josefu lọwọ; ohunkohun ti nwọn ba si ṣe nibẹ̀, on li oluṣe rẹ̀. 23 Onitúbu kò si bojuwò ohun kan ti o wà li ọwọ́ rẹ̀; nitori ti OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati ohun ti o ṣe OLUWA mú u dara.

Genesisi 40

Josẹfu Túmọ̀ Àlá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Meji

1 O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi, li agbọti ọba Egipti ati alasè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Egipti oluwa wọn. 2 Farao si binu si meji ninu awọn ijoye rẹ̀, si olori awọn agbọti, ati si olori awọn alasè. 3 O si fi wọn sinu túbu ninu ile olori ẹṣọ́, sinu túbu ti a gbé dè Josefu si. 4 Olori ẹṣọ́ na si fi Josefu jẹ́ olori wọn; o si nṣe itọju wọn: nwọn si pẹ diẹ ninu túbu na. 5 Awọn mejeji si lá alá kan, olukuluku lá alá tirẹ̀ li oru kanna, olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀, agbọti ati alasè ọba Egipti, ti a dè sinu túba na. 6 Josefu si wọle tọ̀ wọn lọ li owurọ̀, o si wò wọn, si kiyesi i, nwọn fajuro. 7 O si bi awọn ijoye Farao ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ile túbu oluwa rẹ̀ pe, Ẽṣe ti oju nyin fi buru bẹ̃ loni? 8 Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi. 9 Olori agbọti si rọ́ alá tirẹ̀ fun Josefu, o si wi fun u pe, Li oju alá mi, kiyesi i, àjara kan wà niwaju mi, 10 Ati lara àjara na li ẹka mẹta wà; o si rudi, itana rẹ̀ si tú jade; ati ṣiri rẹ̀ si so eso-ájara ti o pọ́n. 11 Ago Farao si wà li ọwọ́ mi: emi si mú eso-àjara na, mo si fún wọn sinu ago Farao, mo si fi ago na lé Farao lọwọ. 12 Josefu si wi fun u pe, Itumọ̀ rẹ̀ li eyi: ẹka mẹta nì, ijọ́ mẹta ni: 13 Ni ijọ́ mẹta oni, ni Farao yio gbe ori rẹ soke yio si mú ọ pada si ipò rẹ: iwọ o si fi ago lé Farao li ọwọ́ gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju nigbati iwọ ti iṣe agbọti rẹ̀. 14 Ṣugbọn ki o ranti mi nigbati o ba dara fun ọ, ki o si fi iṣeun rẹ hàn fun mi, emi bẹ̀ ọ, ki o si da orukọ mi fun Farao, ki o si mú mi jade ninu ile yi. 15 Nitõtọ jíji li a jí mi tà lati ilẹ awọn Heberu wá: ati nihinyi pẹlu, emi kò ṣe nkan ti nwọn fi fi mi sinu ihò-túbu yi. 16 Nigbati olori alasè ri pe itumọ̀ alá na dara, o si wi fun Josefu pe, Emi wà li oju-alá mi pẹlu, si kiyesi i, emi rù agbọ̀n àkara funfun mẹta li ori mi: 17 Ati ninu agbọ̀n ti o wà loke li onirũru onjẹ sisè wà fun Farao; awọn ẹiyẹ si njẹ ẹ ninu agbọ̀n na ti o wà li ori mi. 18 Josefu si dahún o si wipe, itumọ̀ rẹ̀ li eyi: agbọ̀n mẹta nì, ijọ́ mẹta ni. 19 Ni ijọ́ mẹta oni ni Farao yio gbé ori rẹ kuro lara rẹ, yio si so ọ rọ̀ lori igi kan; awọn ẹiyẹ yio si ma jẹ ẹran ara rẹ kuro lara rẹ. 20 O si ṣe ni ijọ́ kẹta, ti iṣe ọjọ́ ibí Farao, ti o sè àse fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ gbogbo: o si gbé ori olori agbọti soke ati ti olori awọn alasè lãrin awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. 21 O si tun mú olori agbọti pada si ipò rẹ̀; on si fi ago lé Farao li ọwọ́: 22 Ṣugbọn olori alasè li o sorọ̀: bi Josefu ti tumọ̀ alá na fun wọn. 23 Ṣugbọn olori agbọti kò ranti Josefu, o gbagbe rẹ̀.

Genesisi 41

Josẹfu Túmọ̀ Àlá Ọba

1 O SI ṣe li opin ọdún meji ṣanṣan, ni Farao lá alá: si kiyesi i, o duro li ẹba odo. 2 Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò. 3 Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na. 4 Awọn abo-malu ti o buru ni wiwò ti o si rù si mú awọn abo-malu meje ti o dara ni wiwò ti o si sanra wọnni jẹ. Bẹ̃ni Farao jí. 5 O si sùn, o si lá alá lẹrinkeji: si kiyesi i, ṣiri ọkà meje yọ lara igi ọkà kan, ti o kún ti o si dara. 6 Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje ti o fori, ti afẹfẹ íla-õrùn rẹ̀ dànu si rú jade lẹhin wọn. 7 Ṣiri meje ti o fori si mú ṣiri meje daradara ti o kún nì jẹ. Farao si jí, si kiyesi i, alá ni. 8 O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao. 9 Nigbana li olori agbọti wi fun Farao pe, Emi ranti ẹ̀ṣẹ mi loni: 10 Farao binu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si fi mi sinu túbu ni ile-túbu olori ẹṣọ́, emi ati olori alasè: 11 Awa si lá alá li oru kanna, emi ati on; awa lá alá olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀. 12 Ọdọmọkunrin kan ara Heberu, ọmọ-ọdọ olori ẹṣọ́, si wà nibẹ̀ pẹlu wa; awa si rọ́ wọn fun u, o si tumọ̀ alá wa fun wa, o tumọ̀ fun olukuluku gẹgẹ bi alá tirẹ̀. 13 O si ṣe bi o ti tumọ̀ fun wa, bẹ̃li o si ri; emi li o mú pada si ipò iṣẹ mi, on li o si sorọ̀. 14 Nigbana ni Farao ranṣẹ o si pè Josefu, nwọn si yara mú u jade kuro ninu ihò-túbu; o si fari rẹ̀, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si tọ̀ Farao wá. 15 Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀. 16 Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao. 17 Farao si wi fun Josefu pe, Li oju-alá mi, kiyesi i, emi duro lori bèbe odò. 18 Si kiyesi i, abo-malu meje ti o sanra, ti o si dara lati wò, jade lati inu odò na wa; nwọn si njẹ ni ẽsu-odò: 19 Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti. 20 Awọn abo-malu ti o rù, ti nwọn si buru ni wiwò, nwọn mú awọn abo-malu meje sisanra iṣaju wọnni jẹ: 21 Nigbati nwọn si jẹ wọn tán, a kò le mọ̀ pe, nwọn ti jẹ wọn: nwọn si buru ni wiwò sibẹ̀ gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Bẹ̃ni mo jí. 22 Mo si ri li oju-alá mi, si kiyesi i, ṣiri ọkà meje jade lara igi ọkà kan, o kún o si dara: 23 Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn: 24 Awọn ṣiri ti o fori si mú awọn ṣiri rere meje nì jẹ; mo si rọ́ ọ fun awọn amoye; ṣugbọn kò sí ẹniti o le sọ ọ fun mi. 25 Josefu si wi fun Farao pe, Ọkan li alá Farao: Ọlọrun ti fi ohun ti on mbọ̀wá iṣe hàn fun Farao. 26 Awọn abo-malu daradara meje nì, ọdún meje ni: ati ṣiri daradara meje nì, ọdún meje ni: ọkan li alá na. 27 Ati awọn abo-malu meje nì ti o rù ti o si buru ni wiwò ti nwọn jade soke lẹhin wọn, ọdún meje ni; ati ṣiri ọkà meje ti o fori nì, ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu nì, ọdún meje ìyan ni yio jasi. 28 Eyi li ohun ti mo ti wi fun Farao pe, ohun ti Ọlọrun mbọ̀wá iṣe, o ti fihàn fun Farao. 29 Kiyesi i, ọdún meje ọ̀pọ mbọ̀ já gbogbo ilẹ Egipti: 30 Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ; 31 A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi. 32 Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan. 33 Njẹ nisisiyi, ki Farao ki o wò amoye ati ọlọgbọ́n ọkunrin kan, ki o si fi i ṣe olori ilẹ Egipti. 34 Ki Farao ki o ṣe eyi, ki o si yàn awọn alabojuto si ilẹ yi, ki nwọn ki o si gbà idamarun ni ilẹ Egipti li ọdún meje ọ̀pọ nì. 35 Ki nwọn ki o si kó gbogbo onjẹ ọdún meje rere nì ti o dé, ki nwọn ki o si tò ọkà jọ si ọwọ́ Farao, ki nwọn ki o si pa onjẹ mọ́ ni ilu wọnni. 36 Onjẹ na ni yio si ṣe isigbẹ fun ilẹ dè ọdún meje ìyan na, ti mbọ̀wá si ilẹ Egipti; ki ilẹ ki o má ba run nitori ìyan na.

Wọ́n fi Josẹfu Jẹ Alákòóso Ilẹ̀ Ijipti

37 Ohun na si dara li oju Farao, ati li oju gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. 38 Farao si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A ha le ri ẹnikan bi irú eyi, ọkunrin ti Ẹmi Ọlọrun mbẹ ninu rẹ̀? 39 Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ: 40 Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ: 41 Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. 42 Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn; 43 O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. 44 Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti. 45 Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti. 46 Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já. 47 Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ. 48 O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀. 49 Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye. 50 A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. 51 Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi. 52 Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi. 53 Ọdún meje ọ̀pọ na ti o wà ni ilẹ Egipti si pari. 54 Ọdún meje ìyan si bẹ̀rẹ si dé, gẹgẹ bi Josefu ti wi: ìyan na si mú ni ilẹ gbogbo; ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Egipti li onjẹ gbé wà. 55 Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe. 56 Ìyan na si wà lori ilẹ gbogbo: Josefu si ṣí gbogbo ile iṣura silẹ, o si ntà fun awọn ara Egipti; ìyan na si nmú si i ni ilẹ Egipti. 57 Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.

Genesisi 42

Àwọn Arakunrin Josẹfu Lọ Ra Ọkà ní Ijipti

1 NIGBATI Jakobu si ri pe ọkà wà ni Egipti, Jakobu wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eṣe ti ẹnyin fi nwò ara nyin li oju? 2 O si wipe, Wò o, mo gbọ́ pe ọkà mbẹ ni Egipti: ẹ sọkalẹ lọ sibẹ̀, ki ẹ si rà fun wa lati ibẹ̀ wá; ki awa ki o le yè, ki a máṣe kú. 3 Awọn arakunrin Josefu mẹwẹwa si sọkalẹ lọ lati rà ọkà ni Egipti. 4 Ṣugbọn Jakobu kò rán Benjamini arakunrin Josefu pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; nitori ti o wipe, Ki ibi ki o má ba bá a. 5 Awọn ọmọ Israeli si wá irà ọkà ninu awọn ti o wá: nitori ìyan na mú ni ilẹ Kenaani. 6 Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ. 7 Josefu si ri awọn arakunrin rẹ̀, o si mọ̀ wọn, ṣugbọn o fi ara rẹ̀ ṣe àjeji fun wọn, o si sọ̀rọ akọ si wọn: o si wi fun wọn pe, Nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, Lati ilẹ Kenaani lati rà onjẹ. 8 Josefu si mọ̀ awọn arakunrin rẹ̀, ṣugbọn awọn kò mọ̀ ọ. 9 Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá. 10 Nwọn si wi fun u pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, ṣugbọn lati rà onjẹ li awọn iranṣẹ rẹ ṣe wá. 11 Ọmọ ẹnikan na ni gbogbo wa iṣe; olõtọ enia li awa, awa iranṣẹ rẹ ki iṣe amí. 12 O si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn lati ri ìhoho ilẹ li ẹ ṣe wá. 13 Nwọn si wipe, Arakunrin mejila li awa iranṣẹ rẹ, ọmọ ẹnikan na ni ilẹ Kenaani: si wò o, eyi abikẹhin si wà lọdọ baba wa loni-oloni, ọkan kò si sí. 14 Josefu si wi fun wọn pe, On na li eyiti mo wi fun nyin pe, Amí li ẹnyin: 15 Eyi bayi li a o fi ridi nyin, nipa ẹmi Farao bi ẹnyin o ti lọ nihin, bikoṣepe arakunrin abikẹhin nyin wá ihinyi. 16 Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe. 17 O si kó gbogbo wọn pọ̀ sinu túbu ni ijọ́ mẹta. 18 Josefu si wi fun wọn ni ijọ́ kẹta pe, Ẹ ṣe eyi ki ẹ si yè; nitori emi bẹ̀ru Ọlọrun. 19 Bi ẹnyin ba ṣe olõtọ enia, ki a mú ọkan ninu awọn arakunrin nyin dè ni ile túbu nyin: ẹ lọ, ẹ mú ọkà lọ nitori ìyan ile nyin. 20 Ṣugbọn ẹ mú arakunrin nyin abikẹhin fun mi wá; bẹ̃li a o si mọ̀ ọ̀rọ nyin li otitọ, ẹ ki yio si kú. Nwọn si ṣe bẹ̃. 21 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Awa jẹbi nitõtọ nipa ti arakunrin wa, niti pe, a ri àrokan ọkàn rẹ̀, nigbati o bẹ̀ wa, awa kò si fẹ́ igbọ́; nitorina ni iyọnu yi ṣe bá wa. 22 Reubeni si da wọn li ohùn pe, Emi kò wi fun nyin pe, Ẹ máṣe ṣẹ̀ si ọmọde na; ẹ kò si fẹ̀ igbọ́? si wò o, nisisiyi, a mbère ẹ̀jẹ rẹ̀. 23 Nwọn kò si mọ̀ pe Josefu gbède wọn; nitori gbedegbẹyọ li o fi mba wọn sọ̀rọ. 24 O si yipada kuro lọdọ wọn, o si sọkun; o si tun pada tọ̀ wọn wá, o si bá wọn sọ̀rọ, o si mú Ṣimeoni ninu wọn, o si dè e li oju wọn.

Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada sí Kenaani

25 Nigbana ni Josefu paṣẹ ki nwọn fi ọkà kún inu àpo wọn, ki nwọn si mú owo olukuluku pada sinu àpo rẹ̀, ki nwọn ki o si fun wọn li onjẹ ọ̀na; bayi li o si ṣe fun wọn. 26 Nwọn si dì ọkà lé kẹtẹkẹtẹ wọn, nwọn si lọ kuro nibẹ̀. 27 Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀. 28 O si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Nwọn mú owo mi pada; si wò o, o tilẹ wà li àpo mi: àiya si fò wọn, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Kili eyiti Ọlọrun ṣe si wa yi? 29 Nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti o bá wọn fun u wipe, 30 Ọkunrin na ti iṣe oluwa ilẹ na, sọ̀rọ lile si wa, o si fi wa pè amí ilẹ na. 31 A si wi fun u pe, Olõtọ, enia li awa; awa ki iṣe amí: 32 Arakunrin mejila li awa, ọmọ baba wa; ọkan kò sí, abikẹhin si wà lọdọ baba wa ni ilẹ Kenaani loni-oloni. 33 Ọkunrin na, oluwa ilẹ na, si wi fun wa pe, Nipa eyi li emi o fi mọ̀ pe olõtọ enia li ẹnyin; ẹ fi ọkan ninu awọn arakunrin nyin silẹ lọdọ mi, ki ẹ si mú onjẹ nitori ìyan ile nyin, ki ẹ si ma lọ. 34 Ẹ si mú arakunrin nyin abikẹhin nì tọ̀ mi wá: nigbana li emi o mọ̀ pe ẹnyin ki iṣe amí, bikoṣe olõtọ enia: emi o si fi arakunrin nyin lé nyin lọwọ, ẹnyin o si ma ṣòwo ni ilẹ yi. 35 O si ṣe, bi nwọn ti ndà àpo wọn, wò o, ìdi owo olukuluku wà ninu àpo rẹ̀: nigbati awọn ati baba wọn si ri ìdi owo wọnni, ẹ̀ru bà wọn. 36 Jakobu baba wọn si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin gbà li ọmọ: Josefu kò sí; Simeoni kò si sí; ẹ si nfẹ́ mú Benjamini lọ: lara mi ni gbogbo nkan wọnyi pọ̀ si. 37 Reubeni si wi fun baba rẹ̀ pe, Pa ọmọ mi mejeji bi emi kò ba mú u fun ọ wá: fi i lé mi lọwọ, emi o si mú u pada fun ọ wá. 38 On si wipe, Ọmọ mi ki yio bá nyin sọkalẹ lọ; nitori arakunrin rẹ̀ ti kú, on nikan li o si kù: bi ibi ba bá a li ọ̀na ti ẹnyin nlọ, nigbana li ẹnyin o fi ibinujẹ mú ewú mi lọ si isà-okú.

Genesisi 43

Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada Lọ sí Ijipti pẹlu Bẹnjamini

1 ÌYAN na si mú ni ilẹ na gidigidi. 2 O si ṣe, nigbati nwọn jẹ ọkà ti nwọn ti múbọ̀ Egipti wá tán, baba wọn wi fun wọn pe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá. 3 Judah si wi fun u pe, ọkunrin na tẹnumọ́ ọ gidigidi fun wa pe, Ẹnyin kò gbọdọ ri oju mi, bikoṣepe arakunrin nyin ba pẹlu nyin. 4 Bi iwọ o ba rán arakunrin wa pẹlu wa, awa o sọkalẹ lọ lati rà onjẹ fun ọ: 5 Ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rán a, awa ki yio sọkalẹ lọ: nitoriti ọkunrin na wi fun wa pe, Ẹnyin ki yio ri oju mi, bikoṣe arakunrin nyin ba pẹlu nyin. 6 Israeli si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi hùwa buburu bẹ̃ si mi, ti ẹnyin fi wi fun ọkunrin na pe, ẹnyin ní arakunrin kan pẹlu? 7 Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá? 8 Judah si wi fun Israeli baba rẹ̀ pe, Rán ọdọmọde na ba mi lọ, awa o si dide, a o lọ; ki awa ki o le yè, ki a má si ṣe kú, ati awa ati iwọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wa. 9 Emi ni yio ṣe onigbọwọ rẹ̀: li ọwọ́ mi ni iwọ o bère rẹ̀; bi emi kò ba mú u pada fun ọ wá, ki nsi mu u duro niwaju rẹ, njẹ emi ni yio rù ẹbi na lailai. 10 Bikoṣepe bi awa ti nṣe ilọra, awa iba sa ti pada bọ̀ lẹrinkeji nisisiyi. 11 Israeli baba wọn si wi fun wọn pe, Njẹ bi bẹ̃ ba ni, eyi ni ki ẹ ṣe, ẹ mú ninu ãyo eso ilẹ yi, sinu ohun-èlo nyin, ki ẹ si mú ọrẹ lọ fun ọkunrin na, ikunra diẹ, ati oyin diẹ, ati turari, ojia, eso pupa, ati eso almondi: 12 Ki ẹ si mú owo miran li ọwọ́ nyin; ati owo ti a mú pada wá li ẹnu àpo nyin, ẹ si tun mú u li ọwọ́ lọ; bọya o le ṣe èṣi: 13 Ẹ mú arakunrin nyin pẹlu, ẹ si dide, ẹ tun pada tọ̀ ọkunrin na lọ: 14 Ki Ọlọrun Olodumare ki o si fun nyin li ãnu niwaju ọkunrin na, ki o le rán arakunrin nyin ọhún wá, ati Benjamini. Bi a ba gbà mi li ọmọ, a gbà mi li ọmọ. 15 Awọn ọkunrin na si mú ọrẹ na, nwọn si mú iṣẹ́po owo meji li ọwọ́ wọn, ati Benjamini; nwọn si dide, nwọn si sọkalẹ lọ si Egipti, nwọn si duro niwaju Josefu. 16 Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri. 17 Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu. 18 Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa. 19 Nwọn si sunmọ iriju ile Josefu, nwọn si bá a sọ̀rọ li ẹnu-ọ̀na ile na, 20 Nwọn si wipe, Alagba, nitõtọ li awa sọkalẹ wá ni iṣaju lati rà onjẹ: 21 O si ṣe, nigbati awa dé ile-èro, ti awa tú àpo wa, si kiyesi i, owo olukuluku wà li ẹnu àpo rẹ̀, owo wa ni pípe ṣánṣan: awa si tun mú u li ọwọ́ pada wá. 22 Owo miran li awa si mú li ọwọ́ wa sọkalẹ wá lati rà onjẹ: awa kò mọ̀ ẹniti o fi owo wa sinu àpo wa. 23 O si wi fun wọn pe, Alafia ni fun nyin, ẹ má bẹ̀ru: Ọlọrun nyin ati Ọlọrun baba nyin, li o fun nyin ni iṣura ninu àpo nyin: owo nyin dé ọwọ́ mi. O si mú Simeoni jade tọ̀ wọn wá. 24 Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ. 25 Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀. 26 Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ. 27 On si bère alafia wọn, o si wipe, Alafia ki baba nyin wà, arugbo na ti ẹnyin wi? o wà lãye sibẹ̀? 28 Nwọn si dahun pe, Ara baba wa, iranṣẹ rẹ le, o wà sibẹ̀. Nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si bù ọlá fun u. 29 O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri Benjamini, aburo rẹ̀, ọmọ iya rẹ̀, o si wipe, Abikẹhin nyin na ti ẹnyin wi fun mi li eyi? o si wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe ojurere si ọ, ọmọ mi. 30 Josefu si yara; nitori ti inu yọ́ ọ si aburo rẹ̀: o wá ibi ti yio gbé sọkun; o si bọ́ si iyẹwu, o si sọkun nibẹ̀. 31 O si bọju rẹ̀, o si jade; o si mú oju dá, o si wipe, Ẹ gbé onjẹ kalẹ. 32 Nwọn si gbé tirẹ̀ kalẹ fun u lọ̀tọ, ati fun wọn lọ̀tọ, ati fun awọn ara Egipti ti o mbá a jẹun lọ̀tọ; nitori ti awọn ara Egipti kò gbọdọ bá awọn enia Heberu jẹun; nitori irira ni fun awọn ara Egipti. 33 Nwọn si joko niwaju rẹ̀, akọ́bi gẹgẹ bi ipò ibí rẹ̀, ati abikẹhin gẹgẹ bi ipò ewe rẹ̀: ẹnu si yà awọn ọkunrin na si ara wọn. 34 O si bù onjẹ fun wọn lati iwaju rẹ̀ lọ: ṣugbọn onjẹ Benjamini jù ti ẹnikẹni wọn lẹrinmarun. Nwọn si mu, nwọn si bá a ṣe ariya.

Genesisi 44

Ife Tí Ó Sọnù

1 O SI fi aṣẹ fun iriju ile rẹ̀, wipe, Fi onjẹ kún inu àpo awọn ọkunrin wọnyi, ìwọn ti nwọn ba le rù, ki o si fi owo olukuluku si ẹnu àpo rẹ̀. 2 Ki o si fi ago mi, ago fadaka nì, si ẹnu àpo abikẹhin, ati owo ọkà rẹ̀. O si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ ti Josefu ti sọ. 3 Bi ojúmọ si ti mọ́, a si rán awọn ọkunrin na lọ, awọn ati awọn kẹtẹkẹtẹ wọn. 4 Nigbati nwọn si jade kuro ni ilu na, ti nwọn kò si jìna, Josefu wi fun iriju rẹ̀ pe, Dide, lepa awọn ọkunrin na; nigbati iwọ ba si bá wọn, wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi fi buburu san rere? 5 Ninu eyi ki oluwa mi ima mu, eyiti o si fi nmọ̀ran? ẹnyin ṣe buburu li eyiti ẹnyin ṣe yi. 6 O si lé wọn bá, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn. 7 Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi. 8 Kiyesi i, owo ti awa ri li ẹnu àpo wa, awa si tun mú pada fun ọ lati ilẹ Kenaani wá: bawo li awa o ṣe jí fadaka tabi wurà ninu ile oluwa rẹ? 9 Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi. 10 O si wipe, Njẹ ki o si ri bẹ̃ gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin: ẹniti a ba ri i li ọwọ́ rẹ̀ on ni yio di ẹrú mi, ẹnyin o si ṣe alailẹṣẹ. 11 Nigbana ni olukuluku nwọn yara sọ̀ àpo rẹ̀ kalẹ, olukuluku nwọn si tú àpo rẹ̀. 12 O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini. 13 Nigbana ni nwọn fà aṣọ wọn ya olukuluku si dì ẹrù lé kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilu. 14 Ati Judah ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si ile Josefu; on sa wà nibẹ̀: nwọn si wolẹ niwaju rẹ̀. 15 Josefu si wi fun wọn pe, Iwa kili eyiti ẹnyin hù yi? ẹnyin kò mọ̀ pe irú enia bi emi a ma mọ̀ran nitõtọ? 16 Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu. 17 On si wipe, Ki a má ri pe emi o ṣe bẹ̃: ṣugbọn ọkunrin na li ọwọ́ ẹniti a ri ago na, on ni yio ṣe ẹrú mi; bi o ṣe ti ẹnyin, ẹ goke tọ̀ baba nyin lọ li alafia.

Juda Bẹ̀bẹ̀ fún Ìdásílẹ̀ Bẹnjamini

18 Nigbana ni Judah sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o sọ gbolohùn ọ̀rọ kan li eti oluwa mi, ki o máṣe binu si iranṣẹ rẹ; bi Farao tikalarẹ̀ ni iwọ sá ri. 19 Oluwa mi bère lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, wipe, Ẹnyin ní baba, tabi arakunrin bi? 20 Awa si wi fun oluwa mi pe, Awa ní baba, arugbo, ati ọmọ kan li ogbologbo rẹ̀, abikẹhin; arakunrin rẹ̀ si kú, on nikanṣoṣo li o si kù li ọmọ iya rẹ̀, baba rẹ̀ si fẹ́ ẹ. 21 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Mú u sọkalẹ tọ̀ mi wá, ki emi ki o le fi oju mi kàn a. 22 Awa si wi fun oluwa mi pe, Ọdọmọde na kò le fi baba rẹ̀ silẹ: nitoripe bi o ba fi i silẹ, baba rẹ̀ yio kú. 23 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Ayaṣebi arakunrin nyin abikẹhin ba bá nyin sọkalẹ wá, ẹnyin ki yio ri oju mi mọ́. 24 O si ṣe nigbati awa goke tọ̀ baba mi iranṣẹ rẹ lọ, awa sọ̀rọ oluwa mi fun u. 25 Baba wa si wipe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá. 26 Awa si wipe, Awa kò le sọkalẹ lọ: bi arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa, njẹ awa o sọkalẹ lọ; nitori ti awa ki o le ri oju ọkunrin na, bikoṣepe arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa. 27 Baba mi iranṣẹ rẹ si wi fun wa pe Ẹnyin mọ̀ pe aya mi bí ọmọ meji fun mi: 28 Ọkan si ti ọdọ mi jade lọ, mo si wipe, Nitõtọ a fà a ya pẹrẹpẹrẹ; emi kò si ri i lati igbana wá: 29 Bi ẹnyin ba si mú eyi lọ lọwọ mi pẹlu, ti ibi kan si ṣe e, ibinujẹ li ẹnyin o fi mú ewú mi lọ si isà-okú. 30 Njẹ nisisiyi, nigbati mo ba dé ọdọ baba mi, iranṣẹ rẹ, ti ọmọde na kò si wà pẹlu wa; bẹ̃ni ẹmi rẹ̀ dìmọ́ ẹmi ọmọde na; 31 Yio si ṣe, bi o ba ri pe ọmọde na kò pẹlu wa, yio kú: awọn iranṣẹ rẹ yio si fi ibinujẹ mú ewú baba wa iranṣẹ rẹ lọ si isà-okú. 32 Nitori iranṣẹ rẹ li o ṣe onigbọwọ ọmọde na fun baba mi wipe, Bi emi kò ba mú u tọ̀ ọ wá, emi ni o gbà ẹbi na lọdọ baba mi lailai. 33 Njẹ nisisiyi emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o joko ni ipò ọmọde na li ẹrú fun oluwa mi; ki o si jẹ ki ọmọde na ki o bá awọn arakunrin rẹ̀ goke lọ. 34 Nitori bi bawo li emi o fi goke tọ̀ baba mi lọ ki ọmọde na ki o ma wà pẹlu mi? ki emi má ba ri ibi ti mbọ̀wá bá baba mi.

Genesisi 45

Josẹfu Farahan Àwọn Arakunrin Rẹ̀

1 NIGBANA ni Josefu kò le mu oju dá mọ́ niwaju gbogbo awọn ti o duro tì i; o si kigbe pe, Ẹ mu ki gbogbo enia ki o jade kuro lọdọ mi. Ẹnikẹni kò si duro tì i, nigbati Josefu sọ ara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. 2 O si sọkun kikan: ati awọn ara Egipti ati awọn ara ile Farao gbọ́. 3 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi ni Josefu; baba mi wà sibẹ̀? awọn arakunrin rẹ̀ kò si le da a lohùn; nitori ti ẹ̀ru bà wọn niwaju rẹ̀. 4 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti. 5 Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là. 6 Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè. 7 Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là. 8 Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti. 9 Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro. 10 Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní. 11 Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju. 12 Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin. 13 Ki ẹnyin ki o si ròhin gbogbo ogo mi ni Egipti fun baba mi, ati ti ohun gbogbo ti ẹnyin ri; ki ẹnyin ki o si yara, ki ẹ si mú baba mi sọkalẹ wá ihin. 14 O si rọ̀mọ́ Benjamini arakunrin rẹ̀ li ọrùn, o si sọkun; Benjamini si sọkun li ọrùn rẹ̀. 15 O si fi ẹnu kò gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li ẹnu, o si sọkun si wọn lara: lẹhin eyini li awọn arakunrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ. 16 A si gbọ́ ìhin na ni ile Farao pe, awọn arakunrin Josefu dé: o si dùn mọ́ Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀. 17 Farao si wi fun Josefu pe, Wi fun awọn arakunrin rẹ, Eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ dì ẹrù lé ẹranko nyin, ki ẹ si lọ si ilẹ Kenaani; 18 Ẹ si mú baba nyin, ati awọn ara ile nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá; emi o si fun nyin li ohun rere ilẹ Egipti, ẹnyin o si ma jẹ ọrá ilẹ yi. 19 Njẹ a fun ọ li aṣẹ, eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ mú kẹkẹ́-ẹrù lati ilẹ Egipti fun awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati fun awọn aya nyin, ki ẹ si mú baba nyin, ki ẹ si wá. 20 Ẹ má si ṣe aniyàn ohun-èlo; nitori ohun rere gbogbo ilẹ Egipti ti nyin ni. 21 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃: Josefu si fi kẹkẹ́-ẹrù fun wọn, gẹgẹ bi aṣẹ Farao, o si fi onjẹ ọ̀na fun wọn. 22 O fi ìparọ-aṣọ fun gbogbo wọn fun olukuluku wọn; ṣugbọn Benjamini li o fi ọdunrun owo fadaka fun, ati ìparọ-aṣọ marun. 23 Bayi li o si ranṣẹ si baba rẹ̀; kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ohun rere Egipti, ati abo-kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ọkà ati àkara ati onjẹ fun baba rẹ̀ li ọ̀na. 24 Bẹ̃li o rán awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si lọ: o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe jà li ọ̀na. 25 Nwọn si goke lati ilẹ Egipti lọ, nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani. 26 Nwọn si wi fun u pe, Josefu mbẹ lãye sibẹ̀, on si ni bãlẹ gbogbo ilẹ Egipti. O si rẹ̀ Jakobu dé inu nitori ti kò gbà wọn gbọ́. 27 Nwọn si sọ ọ̀rọ Josefu gbogbo fun u, ti o wi fun wọn: nigbati o si ri kẹkẹ́-ẹrù ti Josefu rán wá lati fi mú u lọ, ọkàn Jakobu baba wọn sọji: 28 Israeli si wipe, O tó; Josefu ọmọ mi mbẹ lãye sibẹ̀; emi o lọ ki nsi ri i ki emi ki o to kú.

Genesisi 46

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ sí Ijipti

1 ISRAELI si mú ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n ti on ti ohun gbogbo ti o ní, o si dé Beer-ṣeba, o si rú ẹbọ si Ọlọrun Isaaki baba rẹ̀. 2 Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi. 3 O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla. 4 Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé. 5 Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ. 6 Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: 7 Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti. 8 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti, Jakobu ati awọn ọmọ rẹ̀: Reubeni, akọ́bi Jakobu. 9 Ati awọn ọmọ Reubeni; Hanoku, ati Pallu, ati Hesroni, ati Karmi. 10 Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu, ọmọ obinrin ara Kenaani kan. 11 Ati awọn ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari. 12 Ati awọn ọmọ Judah; Eri ati Onani, ati Ṣela, ati Peresi, ati Sera: ṣugbọn Eri on Onani ti kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Peresi ni Hesroni on Hamulu. 13 Ati awọn ọmọ Issakari; Tola, ati Pufa, ati Jobu, ati Simroni. 14 Ati awọn ọmọ Sebuluni; Seredi, ati Eloni, ati Jaleeli. 15 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Lea, ti o bí fun Jakobu ni Padan-aramu, pẹlu Dina ọmọbinrin rẹ̀: gbogbo ọkàn awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, o jẹ́ mẹtalelọgbọ̀n. 16 Ati awọn ọmọ Gadi; Sifioni, ati Haggi, Ṣuni, ati Esboni, Eri, ati Arodi, ati Areli. 17 Ati awọn ọmọ Aṣeri; Jimna, ati Iṣua, ati Isui, ati Beria, ati Sera arabinrin wọn: ati awọn ọmọ Beria; Heberi, ati Malkieli. 18 Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun. 19 Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini. 20 Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u. 21 Ati awọn ọmọ Benjamini; Bela, ati Bekeri, ati Aṣbeli, Gera, ati Naamani, Ehi, ati Roṣi, Muppimu, ati Huppimu, ati Ardi. 22 Wọnyi li awọn ọmọ Rakeli, ti a bí fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ mẹrinla. 23 Ati awọn ọmọ Dani; Huṣimu. 24 Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu. 25 Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje. 26 Gbogbo ọkàn ti o ba Jakobu wá si Egipti, ti o si ti inu Jakobu jade, li àika aya awọn ọmọ Jakobu, ọkàn na gbogbo jẹ́ mẹrindilãdọrin; 27 Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn.

Jakọbu ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ijipti

28 O si rán Judah siwaju rẹ̀ si Josefu ki o kọju wọn si Goṣeni; nwọn si dé ilẹ Goṣeni. 29 Josefu si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si lọ si Goṣeni lọ ipade Israeli baba rẹ̀, o si fi ara rẹ̀ hàn a; on si rọ̀ mọ́ ọ li ọrùn, o si sọkun si i li ọrùn pẹ titi. 30 Israeli si wi fun Josefu pe, Jẹ ki emi ki o kú wayi, bi mo ti ri oju rẹ yi, nitori ti iwọ wà lãye sibẹ̀. 31 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀, ati fun awọn ara ile baba rẹ̀ pe, Emi o goke lọ, emi o si sọ fun Farao, emi o si wi fun u pe, Awọn arakunrin mi, ati awọn ara ile baba mi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, nwọn tọ̀ mi wá; 32 Oluṣọ-agutan si li awọn ọkunrin na, ẹran sisìn ni iṣẹ wọn; nwọn si dà agbo-ẹran ati ọwọ́-ẹran wọn wá, ati ohun gbogbo ti nwọn ní. 33 Yio si ṣe, nigbati Farao ba pè nyin, ti yio si bi nyin pe, Kini iṣẹ nyin? 34 Ki ẹnyin ki o wipe, Òwo awọn iranṣẹ rẹ li ẹran sisìn lati ìgba ewe wa wá titi o fi di isisiyi, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu: ki ẹnyin ki o le joko ni ilẹ Goṣeni; nitori irira li oluṣọ-agutan gbogbo si awọn ara Egipti.

Genesisi 47

1 NIGBANA ni Josefu wọle, o si sọ fun Farao, o si wipe, Baba mi, ati awọn arakunrin mi ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, nwọn ti ilẹ Kenaani wá; si kiyesi i, nwọn mbẹ ni ilẹ Goṣeni. 2 O si mú marun ninu awọn arakunrin rẹ̀, o si mu wọn duro niwaju Farao. 3 Farao si bi awọn arakunrin rẹ̀ pe, Kini iṣẹ nyin? Nwọn si wi fun Farao pe, Oluṣọ-agutan li awọn iranṣẹ rẹ, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu. 4 Nwọn si wi fun Farao pẹlu pe, Nitori ati ṣe atipo ni ilẹ yi li awa ṣe wá; nitori awọn iranṣẹ rẹ kò ní papa-oko tutù fun ọwọ́-ẹran wọn; nitori ti ìyan yi mú gidigidi ni ilẹ Kenaani: njẹ nitorina awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awọn iranṣẹ rẹ ki o joko ni ilẹ Goṣeni. 5 Farao si wi fun Josefu pe, Baba rẹ ati awọn arakunrin rẹ tọ̀ ọ wá: 6 Ilẹ Egipti ni yi niwaju rẹ; ninu ãyo ilẹ ni ki o mu baba ati awọn arakunrin rẹ joko; jẹ ki nwọn ki o joko ni ilẹ Goṣeni: bi iwọ ba si mọ̀ ẹnikẹni ti o li ãpọn ninu wọn, njẹ ki iwọ ki o ṣe wọn li olori lori ẹran-ọsin mi. 7 Josefu si mú Jakobu baba rẹ̀ wọle wá, o si mu u duro niwaju Farao: Jakobu si sure fun Farao. 8 Farao si bi Jakobu pe, Ọdún melo li ọjọ́ aiye rẹ? 9 Jakobu si wi fun Farao pe, Ãdoje ọdún li ọjọ́ atipo mi: diẹ ti on ti buburu li ọdún ọjọ́ aiye mi jẹ́, nwọn kò si ti idé ọdún ọjọ́ aiye awọn baba mi li ọjọ́ atipo wọn. 10 Jakobu si sure fun Farao, o si jade kuro niwaju Farao. 11 Josefu si fi baba rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ joko, o si fun wọn ni iní ni ilẹ Egipti, ni ibi ãyo ilẹ, ni ilẹ Ramesesi, bi Farao ti pa li aṣẹ. 12 Josefu si fi onjẹ bọ́ baba rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ile baba rẹ̀ gẹgẹ bi iye awọn ọmọ wọn.

Àkókò Ìyàn

13 Onjẹ kò si sí ni gbogbo ilẹ; nitori ti ìyan na mú gidigidi, tobẹ̃ ti ilẹ Egipti ati gbogbo ilẹ Kenaani gbẹ nitori ìyan na. 14 Josefu si kó gbogbo owo ti a ri ni ilẹ Egipti ati ni ilẹ Kenaani jọ, fun ọkà ti nwọn rà: Josefu si kó owo na wá si ile Farao. 15 Nigbati owo si tán ni ilẹ Egipti, ati ni ilẹ Kenaani, gbogbo awọn ara Egipti tọ̀ Josefu wá, nwọn si wipe, Fun wa li onjẹ: nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ? owo sa tán. 16 Josefu si wipe, Ẹ mú ẹran nyin wá, emi o si fun nyin li onjẹ dipò ẹran nyin, bi owo ba tán. 17 Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na. 18 Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa: 19 Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro. 20 Bẹ̃ni Josefu rà gbogbo ilẹ Egipti fun Farao; nitori olukuluku awọn ara Egipti li o tà oko rẹ̀, nitori ti ìyan na mú wọn: ilẹ si di ti Farao. 21 Bi o si ṣe ti awọn enia ni, o ṣí wọn si ilu, lati opin ilẹ kan ni Egipti dé opin ilẹ keji. 22 Kìki ilẹ awọn alufa ni kò rà; nitori ti awọn alufa ní ipín ti wọn lati ọwọ́ Farao wá, nwọn si njẹ ipín wọn ti Farao fi fun wọn; nitorina ni nwọn kò fi tà ilẹ wọn. 23 Nigbana ni Josefu wi fun awọn enia pe, Kiyesi i, emi ti rà nyin loni ati ilẹ nyin fun Farao: wò o, irugbìn niyi fun nyin, ki ẹnyin ki o si gbìn ilẹ na. 24 Yio si se, ni ikore ki ẹnyin ki o fi ida-marun fun Farao, ọ̀na mẹrin yio jẹ́ ti ara nyin fun irugbìn oko, ati fun onjẹ nyin, ati fun awọn ara ile nyin, ati onjẹ fun awọn ọmọ nyin wẹrẹ. 25 Nwọn si wipe, Iwọ ti gbà ẹmi wa là: ki awa ki o ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi, awa o si ma ṣe ẹrú Farao. 26 Josefu si ṣe e ni ilana ni ilẹ Egipti titi di oni-oloni pe, Farao ni yio ma ní idamarun; bikoṣe ilẹ awọn alufa nikan ni kò di ti Farao.

Ẹ̀bẹ̀ tí Jakọbu Bẹ̀ kẹ́yìn

27 Israeli si joko ni ilẹ Egipti, ni ilẹ Goṣeni; nwọn si ní iní nibẹ̀, nwọn bísi i, nwọn si rẹ̀ gidigidi. 28 Jakobu si wà li ọdún mẹtadilogun ni ilẹ Egipti; gbogbo ọjọ́ aiye Jakobu si jẹ́ ãdọjọ ọdún o di mẹta: 29 Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti. 30 Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi. 31 O si wipe, Bura fun mi. On si bura fun u. Israeli si tẹriba lori akete.

Genesisi 48

Jakọbu Súre fún Efuraimu ati Manase

1 O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀. 2 Ẹnikan si sọ fun Jakobu, o si wipe, Kiyesi i, Josefu ọmọ rẹ tọ̀ ọ wá: Israeli si gbiyanju, o si joko lori akete. 3 Jakobu si wi fun Josefu pe, Ọlọrun Olodumare farahàn mi ni Lusi ni ilẹ Kenaani, o si sure fun mi, 4 O si wi fun mi pe, Kiyesĩ, Emi o mu ọ bisi i, Emi o mu ọ rẹ̀, Emi o si sọ ọ di ọ̀pọlọpọ enia; Emi o si fi ilẹ yi fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iní titi aiye. 5 Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi. 6 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn. 7 Ati emi, nigbati mo ti Paddani wá, Rakeli kú lọwọ mi ni ilẹ Kenaani li ọ̀na, nigbati o kù diẹ ti a ba fi dé Efrati: emi si sin i nibẹ̀ li ọ̀na Efrati (eyi na ni Betlehemu). 8 Israeli si wò awọn ọmọ Josefu, o si bère pe, Tani wọnyi? 9 Josefu wi fun baba rẹ̀ pe, Awọn ọmọ mi ni, ti Ọlọrun fifun mi nihinyi. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mú wọn wá sọdọ mi, emi o si sure fun wọn. 10 Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra. 11 Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu. 12 Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ. 13 Josefu si mú awọn mejeji, Efraimu li ọwọ́ ọtún rẹ̀ si ọwọ́ òsi Israeli, ati Manasse lọwọ òsi rẹ̀, si ọwọ́ ọtún Israeli, o si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀. 14 Israeli si nà ọwọ́ ọtún rẹ̀, o si fi lé Efraimu ẹniti iṣe aburo li ori, ati ọwọ́ òsi rẹ̀ lé ori Manasse, o mọ̃mọ̀ mu ọwọ́ rẹ̀ lọ bẹ̃: nitori Manasse ni iṣe akọ́bi. 15 O si sure fun Josefu, o si wipe, Ọlọrun, niwaju ẹniti Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi rìn, Ọlọrun na ti o bọ́ mi lati ọjọ́ aiye mi titi di oni, 16 Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye. 17 Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse. 18 Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori. 19 Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède. 20 O si sure fun wọn li ọjọ́ na pe, Iwọ ni Israeli o ma fi sure, wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe nyin bi Efraimu on Manasse: bẹ̃li o fi Efraimu ṣaju Manasse. 21 Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin. 22 Pẹlupẹlu, emi si fi ilẹ-biri kan fun ọ jù awọn arakunrin rẹ lọ, ti mo fi idà ti on ti ọrun mi gbà lọwọ awọn enia Amori.

Genesisi 49

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jakọbu

1 JAKOBU si pè awọn ọmọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ kó ara nyin jọ, ki emi ki o le wi ohun ti yio bá nyin lẹhin-ọla fun nyin. 2 Ẹ kó ara nyin jọ, ki ẹ si gbọ́, ẹnyin ọmọ Jakobu; ki ẹ si fetisi ti Israeli baba nyin. 3 Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara. 4 Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi. 5 Simeoni on Lefi, arakunrin ni nwọn; ohun-èlo ìka ni idà wọn. 6 Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì. 7 Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli. 8 Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ. 9 Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide? 10 Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀. 11 Yio ma so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ ara àjara, ati ọmọ kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ mọ́ ara ãyo àjara; o ti fọ̀ ẹ̀wu rẹ̀ ninu ọtí-waini, ati aṣọ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ eso àjara: 12 Oju rẹ̀ yio pọ́n fun ọtí-waini, ehín rẹ̀ yio si funfun fun wàra. 13 Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni. 14 Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan. 15 O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú. 16 Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli. 17 Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin. 18 Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA! 19 Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn. 20 Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá. 21 Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere. 22 Josefu li ẹka eleso pupọ̀, ẹka eleso pupọ̀ li ẹba kanga; ẹtun ẹniti o yọ si ori ogiri. 23 Awọn tafàtafa bà a ninu jẹ́ pọ̀ju, nwọn si tafà si i, nwọn si korira rẹ̀: 24 Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,) 25 Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu. 26 Ibukún baba rẹ ti jù ibukún awọn baba nla mi lọ, titi dé opin oke aiyeraiye wọnni: nwọn o si ma gbé ori Josefu, ati li atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. 27 Benjamini ni yio ma fàniya bi ikõkò: ni kutukutu ni yio ma jẹ ẹran-ọdẹ rẹ̀, ati li aṣalẹ ni yio ma pín ikogun rẹ̀. 28 Gbogbo wọnyi li awọn ẹ̀ya Israeli mejejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukún tirẹ̀, li o sure fun wọn.

Ikú Jakọbu ati Ìsìnkú Rẹ̀

29 O si kìlọ fun wọn, o si sọ fun wọn pe, A o kó mi jọ pọ̀ pẹlu awọn enia mi: ẹ sin mi pẹlu awọn baba mi ni ihò ti o mbẹ li oko Efroni ara Hitti. 30 Ninu ihò ti o mbẹ ninu oko Makpela ti mbẹ niwaju Mamre, ni ilẹ Kenaani, ti Abrahamu rà pẹlu oko lọwọ Efroni, ara Hitti fun ilẹ-isinku. 31 Nibẹ̀ ni nwọn sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀; nibẹ̀ ni nwọn sin Isaaki ati Rebeka aya rẹ̀; nibẹ̀ ni mo si sin Lea: 32 Lọwọ awọn ọmọ Heti li a ti rà oko na ti on ti ihò ti o wà nibẹ̀. 33 Nigbati Jakobu si ti pari aṣẹ ipa fun awọn ọmọ rẹ̀, o kó ẹsẹ̀ rẹ̀ jọ sori akete, o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.

Genesisi 50

1 JOSEFU si ṣubu lé baba rẹ̀ li oju, o si sọkun si i lara, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 2 Josefu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki nwọn ki o kùn baba on li ọṣẹ: awọn oniṣegun si kùn Israeli li ọṣẹ. 3 Nwọn si kún ogoji ọjọ́ fun u; nitoripe bẹ̃li a ikún ọjọ́ awọn ti a kùn li ọṣẹ: awọn ara Egipti si ṣọ̀fọ rẹ̀ li ãdọrin ọjọ́. 4 Nigbati ọjọ́ ọ̀fọ rẹ̀ kọja, Josefu sọ fun awọn ara ile Farao pe, Njẹ bi emi ba ri ore-ọfẹ li oju nyin emi bẹ̀ nyin, ẹ wi li eti Farao pe, 5 Baba mi mu mi bura wipe, Kiyesi i, emi kú: ni isà mi ti mo ti wà fun ara mi ni ilẹ Kenaani, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o sin mi. Njẹ nitorina emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o goke lọ, ki emi ki o si lọ isin baba mi, emi o si tun pada wá. 6 Farao si wipe, Goke lọ, ki o si sin okú baba rẹ, gẹgẹ bi o ti mu ọ bura. 7 Josefu si goke lọ lati sin baba rẹ̀: ati gbogbo awọn iranṣẹ Farao, ati awọn àlagba ile rẹ̀, ati gbogbo awọn àlagba ilẹ Egipti si bá a goke lọ. 8 Ati gbogbo awọn ara ile Josefu, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ara ile baba rẹ̀: kìki awọn ọmọ wẹ́wẹ wọn, ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ni nwọn fi silẹ ni ilẹ Goṣeni. 9 Ati kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin si bá a goke lọ: ẹgbẹ nlanla si ni ẹgbẹ na. 10 Nwọn si dé ibi ilẹ ipakà Atadi, ti o wà li oke Jordani, nibẹ̀ ni nwọn si gbé fi ohùn rére ẹkún nlanla ṣọ̀fọ rẹ̀: o si ṣọ̀fọ fun baba rẹ̀ li ọjọ́ meje. 11 Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani. 12 Awọn ọmọ rẹ̀ si ṣe bi o ti fi aṣẹ fun wọn: 13 Nitori ti awọn ọmọ rẹ̀ mú u lọ si ilẹ Kenaani, nwọn si sin i ninu ihò oko Makpela, ti Abrahamu rà pẹlu oko fun iní ilẹ isinku, lọwọ Efroni ara Hitti, niwaju Mamre. 14 Josefu si pada wá si Egipti, on ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o bá a goke lọ lati sin baba rẹ̀, lẹhin ti o ti sin baba rẹ̀ tán.

Josẹfu tún Dá Àwọn Arakunrin Rẹ̀ Lọ́kànle

15 Nigbati awọn arakunrin Josefu ri pe baba wọn kú tán, nwọn wipe, Bọya Josefu yio korira wa, yio si gbẹsan gbogbo ibi ti a ti ṣe si i lara wa. 16 Nwọn si rán onṣẹ tọ̀ Josefu lọ wipe, Baba rẹ ti paṣẹ ki o tó kú pe, 17 Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u. 18 Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ pẹlu, nwọn wolẹ niwaju rẹ̀: nwọn si wipe, Wò o, iranṣẹ rẹ li awa iṣe. 19 Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun? 20 Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là. 21 Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.

Ikú Josẹfu

22 Josefu si joko ni Egipti, on ati ile baba rẹ̀: Josefu si wà li ãdọfa ọdún. 23 Josefu si ri awọn ọmọloju Efraimu ti iran kẹta; awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse li a si gbé kà ori ẽkun Josefu pẹlu. 24 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu. 25 Josefu si mu awọn ọmọ Israeli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ. 26 Bẹ̃ni Josefu kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún: nwọn si kùn u li ọṣẹ, a si tẹ́ ẹ sinu posi ni Egipti.

Eksodu 1

Àwọn ará Ijipti fipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́

1 NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀. 2 Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah; 3 Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; 4 Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri. 5 Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti. 6 Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na. 7 Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn. 8 Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu. 9 O si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, kiye si i, enia awọn ọmọ Israeli npọ̀, nwọn si nlagbara jù wa lọ: 10 Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n ba wọn ṣe; ki nwọn ki o máṣe bisi i, yio si ṣe nigbati ogun kan ba ṣẹ̀, nwọn o dàpọ mọ́ awọn ọtá wa pẹlu, nwọn o ma bá wa jà, nwọn o si jade kuro ni ilẹ yi. 11 Nitorina ni nwọn ṣe yàn akoniṣiṣẹ le wọn, lati fi iṣẹ wọn pọ́n wọn loju. Nwọn si kọ́ ilu iṣura fun Farao, Pitomu ati Ramesesi. 12 Bi nwọn si ti npọ́n wọn loju si i, bẹ̃ni nwọn mbisi i, ti nwọn si npọ̀. Inu wọn si bàjẹ́ nitori awọn ọmọ Israeli. 13 Awọn ara Egipti si mu awọn ọmọ Israeli sìn li asìnpa: 14 Nwọn si fi ìsin lile, li erupẹ ati ni briki ṣiṣe, ati ni oniruru ìsin li oko mu aiye wọn korò: gbogbo ìsin wọn ti nwọn mu wọn sìn, asìnpa ni. 15 Ọba Egipti si wi fun awọn iyãgbà Heberu; orukọ ọkan ninu ẹniti ijẹ Ṣifra, ati orukọ ekeji ni Pua: 16 O si wipe, Nigbati ẹnyin ba nṣe iṣẹ iyãgbà fun awọn obinrin Heberu, ti ẹnyin ba ri wọn ni ikunlẹ; bi o ba ṣe ọmọkunrin ni, njẹ ki ẹnyin ki o pa a; ṣugbọn bi o ba ṣe ọmọbinrin ni, njẹ on o yè. 17 Ṣugbọn awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, nwọn kò si ṣe bi ọba Egipti ti fi aṣẹ fun wọn, nwọn si da awọn ọmọkunrin si. 18 Ọba Egipti si pè awọn iyãgbà na, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe irú nkan yi ti ẹnyin si da awọn ọmọkunrin si? 19 Awọn iyãgbà si wi fun Farao pe, nitoriti awọn obinrin Heberu kò ri bi awọn obinrin Egipti; nitoriti ara yá wọn, nwọn a si ti bí ki awọn iyãgbà to wọle tọ̀ wọn lọ. 20 Nitorina Ọlọrun ṣe rere fun awọn iyãgbà na: awọn enia na si mbisi i, nwọn si di alagbara koko. 21 O si ṣe, nitoriti awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, on si kọle fun wọn. 22 Farao si paṣẹ fun gbogbo awọn enia rẹ̀, wipe, Gbogbo ọmọkunrin ti a bí on ni ki ẹnyin gbé jù sinu odò, gbogbo awọn ọmọbinrin ni ki ẹnyin ki o dasi.

Eksodu 2

Ìbí Mose

1 ỌKUNRIN kan ara ile Lefi si lọ, o si fẹ́ ọmọbinrin Lefi kan. 2 Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta. 3 Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na. 4 Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na. 5 Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ si nrìn lọ li ẹba odò na; nigbati o si ri apoti na lãrin koriko odò, o rán ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ kan lati lọ gbé e wá. 6 Nigbati o si ṣi i, o ri ọmọ na; si kiyesi i ọmọde na nsọkun. Inu rẹ̀ si yọ́ si i, o si wipe, Ọkan ninu awọn ọmọ Heberu li eyi. 7 Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ? 8 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Lọ. Ọmọbinrin na si lọ, o si pè iya ọmọ na wá. 9 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Gbé ọmọ yi lọ ki o si tọ́ ọ fun mi, emi o si san owo iṣẹ rẹ fun ọ. Obinrin na si gbé ọmọ na lọ, o si tọ́ ọ. 10 Ọmọ na si dàgba, o si mú u tọ̀ ọmọbinrin Farao wá, on si di ọmọ rẹ̀. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Mose, o si wipe, Nitoriti mo fà a jade ninu omi.

Mose Sá Lọ sí Midiani

11 O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀. 12 O si wò ihin, o wò ọhún, nigbati o si ri pe, kò si ẹnikan, o lù ara Egipti na pa, o si bò o ninu yanrin. 13 Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ? 14 On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀. 15 Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan. 16 Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn. 17 Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn. 18 Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni? 19 Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran. 20 O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun. 21 O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose. 22 On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti nṣe atipo ni ilẹ ajeji. 23 O si ṣe lẹhin ọjọ́ pupọ̀, ti ọba Egipti kú: awọn ọmọ Israeli si ngbin nitori ìsin na, nwọn si ke, igbe wọn si goke tọ̀ Ọlọrun lọ nitori ìsin wọn. 24 Ọlọrun si gbọ́ irora wọn, Ọlọrun si ranti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, pẹlu Isaaki, ati pẹlu Jakobu. 25 Ọlọrun si bojuwò awọn ọmọ Israeli, Ọlọrun si mọ̀ ọ fun wọn.

Eksodu 3

Ọlọrun Pe Mose

1 MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun. 2 Angeli OLUWA si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati inu ãrin igbẹ̀: on si wò, si kiyesi i, iná njó igbẹ́, igbẹ́ na kò si run. 3 Mose si wipe, Njẹ emi o yipada si apakan, emi o si wò iran nla yi, ẽṣe ti igbẹ́ yi kò run. 4 Nigbati OLUWA ri pe, o yipada si apakan lati wò o, Ọlọrun kọ si i lati inu ãrin igbẹ́ na wá, o si wipe, Mose, Mose. On si dahun pe, Emi niyi. 5 O si wipe, Máṣe sunmọ ihin: bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ, nitori ibiti iwọ gbé duro si nì, ilẹ mimọ́ ni. 6 O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun. 7 OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn; 8 Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi. 9 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, igbe awọn ọmọ Israeli dé ọdọ mi; emi si ti ri pẹlu, wahala ti awọn ọba Egipti nwahala wọn. 10 Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki iwọ ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israeli, lati Egipti jade wá. 11 Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá? 12 O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi. 13 Mose si wi fun Ọlọrun pe, Kiyesi i, nigbati mo ba dé ọdọ awọn ọmọ Israeli, ti emi o si wi fun wọn pe, Ọlọrun awọn baba nyin li o rán mi si nyin; ti nwọn o si bi mi pe, Orukọ rẹ̀? kili emi o wi fun wọn? 14 Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin. 15 Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran. 16 Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti: 17 Emi si ti wipe, Emi o mú nyin goke jade ninu ipọnju Egipti si ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin. 18 Nwọn o si fetisi ohùn rẹ: iwọ o si wá, iwọ ati awọn àgba Israeli, sọdọ ọba Egipti, ẹnyin o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu pade wa: jẹ ki a lọ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki awa ki o le rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. 19 Emi si mọ̀ pe ọba Egipti ki yio jẹ ki ẹnyin ki o lọ, ki tilẹ iṣe nipa ọwọ́ agbara. 20 Emi o si nà ọwọ́ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlù Egipti ti emi o ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin eyinì li on o to jọwọ nyin lọwọ lọ. 21 Emi o si fi ojurere fun awọn enia yi li oju awọn ara Egipti: yio si ṣe, nigbati ẹnyin o lọ, ẹnyin ki yio lọ li ofo: 22 Olukuluku obinrin ni yio si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ, lọwọ aladugbo rẹ̀, ati lọwọ ẹniti o nṣe atipo ninu ile rẹ̀: ẹnyin o si fi wọn si ara awọn ọmọkunrin nyin, ati si ara awọn ọmọbinrin nyin: ẹnyin o si kó ẹrù awọn ara Egipti.

Eksodu 4

Ọlọrun Fún Mose ní Agbára Ìyanu

1 MOSE si dahùn o si wipe, Ṣugbọn kiyesi i, nwọn ki yio gbà mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn ki yio fetisi ohùn mi: nitoriti nwọn o wipe, OLUWA kò farahàn ọ. 2 OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni. 3 O si wi fun u pe, Sọ ọ si ilẹ. On si sọ ọ si ilẹ, o si di ejò; Mose si sá kuro niwaju rẹ̀. 4 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ ki o si mú u ni ìru: (On si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si di ọpá si i li ọwọ́:) 5 Ki nwọn ki o le gbàgbọ́ pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o farahàn ọ. 6 OLUWA si tun wi fun u pe, Fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀: nigbati o si fà a yọ jade, si kiyesi i, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, o fún bi ẹ̀gbọn owu. 7 O si wipe, Tun fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. (O si tun fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀; o si fà a yọ jade li àiya rẹ̀; si kiyesi i, o si pada bọ̀ bi ẹran ara rẹ̀.) 8 Yio si ṣe, bi nwọn kò ba gbà ọ gbọ́, ti nwọn kò si fetisi ohùn iṣẹ-àmi iṣaju, njẹ nwọn o gbà ohùn iṣẹ-àmi ikẹhin gbọ́. 9 Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ. 10 Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo. 11 OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́? 12 Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi. 13 On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán. 14 Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀. 15 Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe. 16 On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u. 17 Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi.

Mose Pada Lọ sí Ijipti

18 Mose si lọ, o si pada tọ̀ Jetro ana rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nlọ ki emi si pada tọ̀ awọn arakunrin mi ti o wà ni Egipti, ki emi ki o si wò bi nwọn wà li ãye sibẹ̀. Jetro si wi fun Mose pe, Mã lọ li alafia. 19 OLUWA si wi fun Mose ni Midiani pe, Lọ, pada si Egipti: nitori gbogbo enia ti nwá ẹmi rẹ ti kú tán. 20 Mose si mú aya rẹ̀ ati awọn ọmọ-ọkunrin rẹ̀, o si gbé wọn gùn kẹtẹkẹtẹ kan, o si pada si ilẹ Egipti: Mose si mú ọpá Ọlọrun na li ọwọ́ rẹ̀. 21 OLUWA si wi fun Mose pe, Nigbati iwọ ba dé Egipti, kiyesi i ki iwọ ki o ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu, ti mo filé ọ lọwọ, niwaju Farao, ṣugbọn emi o mu àiya rẹ̀ le, ti ki yio fi jẹ ki awọn enia na ki o lọ. 22 Iwọ o si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA wi, Ọmọ mi ni Israeli, akọ́bi mi: 23 Emi si ti wi fun ọ pe, Jẹ ki ọmọ mi ki o lọ, ki o le ma sìn mi; iwọ si ti kọ̀ lati jẹ ki o lọ: kiyesi i, emi o pa ọmọ rẹ, ani akọ́bi rẹ. 24 O si ṣe li ọ̀na ninu ile-èro, li OLUWA pade rẹ̀, o si nwá ọ̀na lati pa a. 25 Nigbana ni Sippora mú okuta mimú, o si kọ ọmọ rẹ̀ ni ilà abẹ, o si sọ ọ si ẹsẹ̀ Mose, o si wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ fun mi nitõtọ. 26 Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. Nigbana ni Sippora wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ nitori ikọlà na. 27 OLUWA si wi fun Aaroni pe, Lọ si ijù lọ ipade Mose. On si lọ, o si pade rẹ̀ li oke Ọlọrun, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 28 Mose si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o rán a fun Aaroni, ati gbogbo aṣẹ iṣẹ-àmi ti o fi fun u. 29 Mose ati Aaroni si lọ, nwọn si kó gbogbo àgba awọn ọmọ Israeli jọ: 30 Aaroni si sọ gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ-àmi na li oju awọn enia na. 31 Awọn enia na si gbàgbọ́: nigbati nwọn si gbọ́ pe, OLUWA ti bẹ̀ awọn ọmọ Israeli wò, ati pe o si ti ri ipọnju wọn, nigbana ni nwọn tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn.

Eksodu 5

Mose ati Aaroni níwájú Ọba Ijipti

1 LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù. 2 Farao si wipe, Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ lati jẹ ki Israeli ki o lọ? Emi kò mọ̀ OLUWA na, bẹ̃li emi ki yio jẹ ki Israeli ki o lọ. 3 Nwọn si wipe, Ọlọrun awọn Heberu li o pade wa: awa bẹ̀ ọ, jẹ ki a lọ ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa; ki o má ba fi ajakalẹ-àrun tabi idà kọlù wa. 4 Ọba Egipti si wi fun wọn pe, Mose ati Aaroni, nitori kili ẹnyin ṣe dá awọn enia duro ninu iṣẹ wọn? ẹ lọ si iṣẹ nyin. 5 Farao si wipe, Kiyesi i awọn enia ilẹ yi pọ̀ju nisisiyi, ẹnyin si mu wọn simi kuro ninu iṣẹ wọn. 6 Farao si paṣẹ li ọjọ́ na fun awọn akoniṣiṣẹ awọn enia, ati fun awọn olori wọn wipe, 7 Ẹnyin kò gbọdọ fun awọn enia na ni koriko mọ́ lati ma ṣe briki, bi ìgba atẹhinwá: jẹ ki nwọn ki o ma lọ ṣà koriko fun ara wọn. 8 Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa. 9 Ẹ jẹ ki iṣẹ ki o wuwo fun awọn ọkunrin na, ki nwọn ki o le ma ṣe lãlã ninu rẹ̀; ẹ má si ṣe jẹ ki nwọn ki o fiyesi ọ̀rọ eke. 10 Awọn akoniṣiṣẹ enia na si jade, ati awọn olori wọn, nwọn si sọ fun awọn enia na, pe, Bayi ni Farao wipe, Emi ki yio fun nyin ni koriko mọ́. 11 Ẹ lọ, ẹ wá koriko nibiti ẹnyin gbé le ri i: ṣugbọn a ki yio ṣẹ nkan kù ninu iṣẹ nyin. 12 Bẹ̃li awọn enia na si tuka kiri ká gbogbo ilẹ Egipti lati ma ṣà idi koriko ni ipò koriko. 13 Awọn akoniṣiṣẹ lé wọn ni ire wipe, Ẹ ṣe iṣẹ nyin pé, iṣẹ ojojumọ́ nyin, bi igbati koriko mbẹ. 14 Ati awọn olori awọn ọmọ Israeli, ti awọn akoniṣiṣẹ Farao yàn lé wọn, li a nlù, ti a si mbilère pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò ṣe iṣẹ nyin pé ni briki ṣiṣe li ana ati li oni, bi ìgba atẹhinwá? 15 Nigbana li awọn olori awọn ọmọ Israeli wá, nwọn si ke tọ̀ Farao wipe, Ẽṣe ti iwọ fi nṣe awọn iranṣẹ rẹ bayi? 16 A kò fi koriko fun awọn iranṣẹ rẹ, nwọn si nwi fun wa pe, Ẹ ṣe briki: si kiyesi i, a nlù awọn iranṣẹ rẹ; ṣugbọn lọwọ awọn enia rẹ li ẹbi wà. 17 Ṣugbọn on wipe, Ẹnyin ọlẹ, ẹnyin ọlẹ: nitorina li ẹ ṣe wipe, Jẹ ki a lọ ṣẹbọ si OLUWA. 18 Njẹ ẹ lọ nisisiyi, ẹ ṣiṣẹ; a ki yio sá fi koriko fun nyin, sibẹ̀ iye briki nyin yio pé. 19 Awọn olori awọn ọmọ Israeli si ri pe, ọ̀ran wọn kò li oju, lẹhin igbati a wipe, Ẹ ki o dinkù ninu iye briki nyin ojojumọ́. 20 Nwọn si bá Mose on Aaroni, ẹniti o duro lati pade wọn bi nwọn ti nti ọdọ Farao jade wá: 21 Nwọn si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o wò nyin, ki o si ṣe idajọ; nitoriti ẹnyin mu wa di okú-õrùn li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀, lati fi idá lé wọn lọwọ lati pa wa.

Mose Ráhùn sí OLUWA

22 Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wi fun u pe, OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi? 23 Nitori igbati mo ti tọ̀ Farao wá lati sọ̀rọ li orukọ rẹ, buburu li o ti nṣe si awọn enia yi; bẹ̃ni ni gbigbà iwọ kò si gbà awọn enia rẹ.

Eksodu 6

Ọlọrun Pe Mose

1 NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ́ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ́ agbara li on o fi tì wọn jade kuro ni ilẹ rẹ̀. 2 Ọlọrun si sọ fun Mose, o si wi fun u pe, Emi ni JEHOFA: 3 Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, li orukọ Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn orukọ mi JEHOFA, ni nwọn kò fi mọ̀ mi. 4 Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo. 5 Emi si ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sìn; emi si ti ranti majẹmu mi. 6 Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde: 7 Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti. 8 Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA. 9 Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile. 10 OLUWA si sọ fun Mose pe, 11 Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀. 12 Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète? 13 OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti.

Àkọsílẹ̀ Ìran Mose ati Ti Aaroni

14 Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni. 15 Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu ọmọ obinrin ara Kénaani; wọnyi ni idile Simeoni. 16 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Lefi ni iran wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari: ọdún aiye Lefi si jẹ́ mẹtadilogoje. 17 Awọn ọmọ Gerṣoni; Libni, ati Ṣimei, ni idile wọn. 18 Ati awọn ọmọ Kohati; Amramu ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli ọdún aiye Kohati si jẹ́ ãdoje o le mẹta. 19 Ati awọn ọmọ Merari; Mahali, ati Muṣi. Wọnyi ni idile Lefi ni iran wọn. 20 Amramu si fẹ́ Jokebedi arabinrin baba rẹ̀ li aya, on li o si bi Aaroni ati Mose fun u: ọdún aiye Amramu si jẹ́ mẹtadilogoje. 21 Ati awọn ọmọ Ishari; Kora, ati Nefegi, ati Sikri. 22 Ati awọn ọmọ Ussieli; Miṣaeli, ati Elsafani, ati Sitri. 23 Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u. 24 Ati awọn ọmọ Kora; Assiri, ati Elkana, ati Abiasafu; wọnyi ni idile awọn ọmọ Kora. 25 Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn. 26 Wọnyi ni Aaroni on Mose na, ẹniti OLUWA sọ fun pe, Ẹ mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn. 27 Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na.

Àṣẹ Tí OLUWA Pa fún Mose ati Aaroni

28 O si ṣe li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ ni ilẹ Egipti, 29 Ni OLUWA sọ fun Mose wipe, Emi li OLUWA: sọ gbogbo eyiti mo wi fun ọ fun Farao ọba Egipti. 30 Mose si wi niwaju OLUWA pe, Kiyesi i, alaikọlà ète li emi, Farao yio ha ti ṣe fetisi ti emi?

Eksodu 7

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi fi ọ ṣe ọlọrun fun Farao: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma ṣe wolĩ rẹ. 2 Iwọ o sọ gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma sọ fun Farao pe, ki o rán awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ rẹ̀. 3 Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. 4 Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti. 5 Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn. 6 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe. 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún, Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún o le mẹta, nigbati nwọn sọ̀rọ fun Farao.

Ọ̀pá Aaroni

8 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 9 Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò. 10 Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò. 11 Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ. 12 Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì. 13 Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú ṣẹ̀ ní Ijipti

14 OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ. 15 Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ. 16 Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́. 17 Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ. 18 Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na. 19 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta. 20 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ. 21 Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, 22 Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. 23 Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu. 24 Gbogbo awọn ara Egipti si wàlẹ yi odò na ká fun omi mimu; nitoriti nwọn kò le mu ninu omi na. 25 Ọjọ́ meje si pé, lẹhin igbati OLUWA lù odò na.

Eksodu 8

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Tọ̀ Farao lọ, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi. 2 Bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki nwọn ki o lọ, kiyesi i, emi o fi ọpọlọ kọlù gbogbo ẹkùn rẹ: 3 Odò yio si bi ọpọlọ jade li ọ̀pọlọpọ, nwọn o si goke, nwọn o si wá sinu ile rẹ, ati sinu ibùsun rẹ, ati sori akete rẹ, ati sinu ile awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu ãro rẹ, ati sinu ọpọ́n ìpo-iyẹfun rẹ: 4 Awọn ọpọlọ na yio si gùn ọ lara, ati lara awọn enia rẹ, ati lara gbogbo awọn iranṣẹ rẹ. 5 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Nà ọwọ́ rẹ pẹlu ọpá rẹ sori odò wọnni, sori omi ṣiṣàn, ati sori ikojọpọ̀ omi, ki o si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti. 6 Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ sori omi Egipti; awọn ọpọlọ si goke wá, nwọn si bò ilẹ Egipti. 7 Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃, nwọn si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti. 8 Nigbana ni Farao pè Mose ati Aaroni, o si wipe, Ẹ bẹ̀ OLUWA, ki o le mú awọn ọpọlọ kuro lọdọ mi, ati kuro lọdọ awọn enia mi; emi o si jẹ ki awọn enia na ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣẹbọ si OLUWA. 9 Mose si wi fun Farao pe, Paṣẹ fun mi: nigbawo li emi o bẹ̀bẹ fun ọ, ati fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun awọn enia rẹ, lati run awọn ọpọlọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ki nwọn ki o kù ni kìki odò nikan? 10 On si wipe, Li ọla. O si wipe, Ki o ri bi ọ̀rọ rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe, kò sí ẹniti o dabi OLUWA Ọlọrun wa. 11 Awọn ọpọlọ yio si lọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ; ni kìki odò ni nwọn o kù si. 12 Mose ati Aaroni si jade kuro lọdọ Farao: Mose si kigbe si OLUWA nitori ọpọlọ ti o ti múwa si ara Farao. 13 OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; awọn ọpọlọ na si kú kuro ninu ile, ninu agbalá, ati kuro ninu oko. 14 Nwọn si kó wọn jọ li òkiti-òkiti: ilẹ na si nrùn. 15 Ṣugbọn nigbati Farao ri pe isimi wà, o mu àiya rẹ̀ le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. 16 OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti. 17 Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti. 18 Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran. 19 Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. 20 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi. 21 Bi iwọ kò ba si jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, emi o rán ọwọ́ eṣinṣin si ọ, ati sara iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu awọn ile rẹ: gbogbo ile awọn ara Egipti ni yio si kún fun ọwọ́ eṣinṣin, ati ilẹ ti nwọn gbé wà pẹlu. 22 Li ọjọ́ na li emi o yà ilẹ Goṣeni sọ̀tọ, ninu eyiti awọn enia mi tẹ̀dó si, ti eṣinṣin ki yio sí nibẹ̀; nitori ki iwọ ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA lãrin ilẹ aiye. 23 Emi o si pàla si agbedemeji awọn enia mi ati awọn enia rẹ: li ọla ni iṣẹ-amì yi yio si wà. 24 OLUWA si ṣe bẹ̃; ọwọ́ eṣinṣin ọ̀pọlọpọ si dé sinu ile Farao, ati sinu ile awọn iranṣẹ rẹ̀: ati ni gbogbo ilẹ Egipti, ilẹ na bàjẹ́ nitori ọwọ́ eṣinṣin wọnni. 25 Farao si ranṣẹ pè Mose ati Aaroni o si wipe; Ẹ ma lọ ṣẹbọ si Ọlọrun nyin ni ilẹ yi. 26 Mose si wipe, Kò tọ́ lati ṣe bẹ̃; nitori awa o fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ si OLUWA Ọlọrun wa: wò o, awa le fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ li oju wọn, nwọn ki yio ha sọ wa li okuta? 27 Awa o lọ ni ìrin ijọ́ mẹta sinu ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa, bi on o ti paṣẹ fun wa. 28 Farao si wipe, Emi o jẹ ki ẹnyin lọ, ki ẹ le rubọ si OLUWA Ọlọrun nyin ni ijù; kìki ki ẹnyin ki o máṣe lọ jìna jù: ẹ bẹ̀bẹ fun mi. 29 Mose si wipe, Kiyesi i, emi njade lọ kuro lọdọ rẹ, emi o si bẹ̀ OLUWA ki ọwọ́ eṣinṣin wọnyi ki o le ṣi kuro lọdọ Farao, kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀, li ọla: kìki ki Farao ki o máṣe ẹ̀tan mọ́ li aijẹ ki awọn enia na ki o lọ rubọ si OLUWA. 30 Mose si jade kuro lọdọ Farao, o si bẹ̀ OLUWA. 31 OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; o si ṣi ọwọ́ eṣinṣin na kuro lọdọ Farao, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀; ọkan kò kù. 32 Farao si mu àiya rẹ̀ le nigbayi pẹlu, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.

Eksodu 9

1 NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn le sìn mi. 2 Nitoripe, bi iwọ ba kọ̀ lati jẹ ki nwọn lọ, ti iwọ si da wọn duro sibẹ̀, 3 Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀. 4 OLUWA yio si pàla si agbedemeji ẹran-ọ̀sin Israeli ati ẹran-ọ̀sin Egipti: kò si ohun kan ti yio kú ninu gbogbo eyiti iṣe ti awọn ọmọ Israeli. 5 OLUWA si dá akokò kan wipe, Li ọla li OLUWA yio ṣe nkan yi ni ilẹ yi. 6 OLUWA si ṣe nkan na ni ijọ́ keji, gbogbo ẹran-ọ̀sin Egipti si kú: ṣugbọn ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli ọkanṣoṣọ kò si kú. 7 Farao si ranṣẹ, si kiyesi i, ọkanṣoṣo kò kú ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli. Àiya Farao si le, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ. 8 OLUWA si wi fun Mose ati fun Aaroni pe, Bù ikunwọ ẽru ninu ileru, ki Mose ki o kù u si oju-ọrun li oju Farao. 9 Yio si di ekuru lẹbulẹbu ni gbogbo ilẹ Egipti, yio si di õwo ti yio ma tú pẹlu ileròro lara enia, ati lara ẹran, ká gbogbo ilẹ Egipti. 10 Nwọn si bù ẽru ninu ileru, nwọn duro niwaju Farao; Mose si kù u si oke ọrun; o si di õwo ti o ntú jade pẹlu ileròro lara enia ati lara ẹran. 11 Awọn alalupayida kò si le duro niwaju Mose nitori õwo wọnni; nitoriti õwo na wà lara awọn alalupayida, ati lara gbogbo awọn ara Egipti. 12 OLUWA si mu àiya Farao le, kò si gbọ́ ti wọn; bi OLUWA ti sọ fun Mose. 13 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ ki nwọn le sìn mi. 14 Nitori ìgba yi li emi o rán gbogbo iyọnu mi si àiya rẹ, ati sara awọn iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe kò si ẹlomiran bi emi ni gbogbo aiye. 15 Nitori nisisiyi, emi iba nà ọwọ́ mi, ki emi ki o le fi ajakalẹ-àrun lù ọ, ati awọn enia rẹ; a ba si ti ke ọ kuro lori ilẹ. 16 Ṣugbọn nitori eyi pãpa li emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a le ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. 17 Titi di isisiyi iwọ ngbé ara rẹ ga si awọn enia mi pe, iwọ ki yio jẹ ki nwọn ki o lọ? 18 Kiyesi i, li ọla li akokò yi, li emi o mu ọ̀pọ yinyin rọ̀ si ilẹ, irú eyiti kò ti si ni Egipti lati ipilẹṣẹ rẹ̀ titi o fi di isisiyi. 19 Njẹ nisisiyi ranṣẹ, ki o si kó ẹran rẹ bọ̀, ati ohun gbogbo ti o ni ninu oko; nitori olukuluku enia ati ẹran ti a ba ri li oko, ti a kò si múbọ̀ wá ile, yinyin yio bọ lù wọn, nwọn o si kú. 20 Ẹniti o bẹ̀ru ọ̀rọ OLUWA ninu awọn iranṣẹ Farao, mu ki awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ sá padà wá ile: 21 Ẹniti kò si kà ọ̀rọ OLUWA si, jọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ si oko. 22 OLUWA si sọ fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si oke ọrun, ki yinyin ki o le bọ́ si gbogbo ilẹ Egipti, sara enia, ati sara ẹranko, ati sara eweko igbẹ́ gbogbo, já gbogbo ilẹ Egipti. 23 Mose si nà ọpá rẹ̀ si ọrun: OLUWA si rán ãra ati yinyin, iná na si njó lori ilẹ; OLUWA si rọ̀ yinyin sori ilẹ Egipti. 24 Yinyin si bọ́, iná si dàpọ mọ́ yinyin na, o papọ̀ju, irú rẹ̀ kò si ri ni gbogbo ilẹ Egipti lati ìgba ti o ti di orilẹ-ède. 25 Yinyin na si lù ohun gbogbo ti o wà ninu oko bolẹ, ati enia ati ẹranko, já gbogbo ilẹ Egipti; yinyin na si lù gbogbo eweko bolẹ, o si fà gbogbo igi igbẹ́ ya. 26 Ni kìki ilẹ Goṣeni, nibiti awọn ọmọ Israeli gbé wà, ni yinyin kò si. 27 Farao si ranṣẹ, o si pè Mose ati Aaroni, o si wi fun wọn pe, Emi ṣẹ̀ nigbayi: OLUWA li olododo, ẹni buburu si li emi ati awọn enia mi. 28 Ẹ bẹ̀ OLUWA (o sa to) ki ãra nla ati yinyin wọnyi ki o máṣe si mọ́; emi o si jẹ ki ẹ ma lọ; ẹ ki yio si duro mọ́. 29 Mose si wi fun u pe, Bi mo ba ti jade ni ilu, emi o tẹ́ ọwọ́ mi si OLUWA; ãra yio si dá, bẹ̃ni yinyin ki yio si mọ́; ki iwọ ki o le mọ̀ pe ti OLUWA li aiye. 30 Ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni ati ti awọn iranṣẹ rẹ, emi mọ̀ pe sibẹ, ẹnyin kò ti ibẹ̀ru OLUWA Ọlọrun. 31 A si lù ọgbọ́ ati ọkà barle bolẹ; nitori ọkà barle wà ni ipẹ́, ọgbọ́ si rudi. 32 Ṣugbọn alikama ati ọkà (rie) li a kò lù bolẹ: nitoriti nwọn kò ti idàgba. 33 Mose si jade kuro lọdọ Farao sẹhin ilu, o si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ si OLUWA; ãra ati yinyin si dá, bẹ̃li òjo kò si rọ̀ si ilẹ̀ mọ́. 34 Nigbati Farao ri pe, òjo ati yinyin ati ãra dá, o ṣẹ̀ si i, o si sé àiya rẹ̀ le, on ati awọn iranṣẹ rẹ̀. 35 Àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ; bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.

Eksodu 10

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ: nitoriti mo mu àiya rẹ̀ le, ati àiya awọn iranṣẹ rẹ̀, ki emi ki o le fi iṣẹ-àmi mi wọnyi hàn niwaju rẹ̀: 2 Ati ki iwọ ki o le wi li eti ọmọ rẹ, ati ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun ti mo ṣe ni Egipti, ati iṣẹ-àmi mi ti mo ṣe ninu wọn; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA. 3 Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si wi fun u pe, Bayi li OLUWA Ọlọrun Heberu wi, Iwọ o ti kọ̀ pẹ tó lati rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi? jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi. 4 Ṣugbọn bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, li ọla li emi o mú eṣú wá si ẹkùn rẹ: 5 Nwọn o si bò oju ilẹ ti ẹnikan ki yio fi le ri ilẹ: nwọn o si jẹ ajẹkù eyiti o bọ́, ti o kù fun nyin lọwọ yinyin, yio si jẹ igi nyin gbogbo ti o nruwe ninu oko. 6 Nwọn o si kún ile rẹ, ati ile awọn iranṣẹ rẹ gbogbo, ati ile awọn ara Egipti gbogbo; ti awọn baba rẹ, ati awọn baba baba rẹ kò ri ri, lati ìgba ọjọ́ ti nwọn ti wà lori ilẹ titi o fi di oni-oloni. O si yipada, o jade kuro lọdọ Farao. 7 Awọn iranṣẹ Farao si wi fun u pe, ọkunrin yi yio ti ṣe ikẹkùn si wa pẹ to? jẹ ki awọn ọkunrin na ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn OLUWA Ọlọrun wọn: iwọ kò ti imọ̀ pe Egipti run tán? 8 A si tun mú Mose ati Aaroni wá sọdọ Farao: o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ sìn OLUWA Ọlọrun nyin; ṣugbọn awọn tani yio ha lọ? 9 Mose si wipe, Awa o lọ ati ewe ati àgba, ati awọn ọmọkunrin wa ati awọn ọmọbinrin wa, pẹlu awọn agbo, ati ọwọ́-ẹran wa li awa o lọ; nitori ajọ OLUWA ni fun wa: 10 O si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o pẹlu nyin bẹ̃, bi emi o ti jẹ ki ẹ lọ yi, ati awọn ewe nyin: ẹ wò o; nitori ibi mbẹ niwaju nyin. 11 Bẹ̃kọ: ẹnyin ọkunrin ẹ lọ, ki ẹ si sìn OLUWA; eyinì li ẹnyin sá nfẹ́. Nwọn si lé wọn jade kuro niwaju Farao. 12 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ sori ilẹ Egipti nitori eṣú, ki nwọn ki o le wá sori ilẹ Egipti, ki nwọn ki o si le jẹ gbogbo eweko ilẹ yi, gbogbo eyiti yinyin ti kù silẹ. 13 Mose si nà ọpá rẹ̀ si ori ilẹ Egipti, OLUWA si mu afẹfẹ ìla-õrùn kan fẹ́ si ori ilẹ na, ni gbogbo ọsán na, ati gbogbo oru na; nigbati o di owurọ̀, afẹfẹ ila-õrùn mú awọn eṣú na wá. 14 Awọn eṣú na si goke sori ilẹ Egipti gbogbo, nwọn si bà si ẹkùn Egipti gbogbo; nwọn papọ̀ju, kò si irú eṣú bẹ̃ ṣaju wọn, bẹ̃ni lẹhin wọn irú wọn ki yio si si. 15 Nitoriti nwọn bò oju ilẹ gbogbo, tobẹ̃ ti ilẹ fi ṣú; nwọn si jẹ gbogbo eweko ilẹ na, ati gbogbo eso igi ti yinyin kù silẹ: kò si kù ohun tutù kan lara igi, tabi lara eweko igbẹ́, já gbogbo ilẹ Egipti. 16 Nigbana ni Farao ranṣẹ pè Mose ati Aaroni kánkan; o si wipe, Emi ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ati si nyin. 17 Njẹ nitorina emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ẹ̀ṣẹ mi jì lẹ̃kanṣoṣo yi, ki ẹ si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun nyin, ki o le mú ikú yi kuro lọdọ mi. 18 On si jade kuro niwaju Farao, o si bẹ̀ OLUWA. 19 OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti. 20 Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ. 21 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà. 22 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si ọrun; òkunkun biribiri si ṣú ni gbogbo ilẹ Egipti ni ijọ́ mẹta: 23 Nwọn kò ri ara wọn, bẹ̃li ẹnikan kò si dide ni ipò tirẹ̀ ni ijọ́ mẹta: ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Israeli li o ni imọle ni ibugbé wọn. 24 Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu. 25 Mose si wipe, Iwọ kò le ṣaima fun wa li ohun ẹbọ pẹlu ati ẹbọ sisun, ti awa o fi rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. 26 Ẹran-ọ̀sin wa yio si bá wa lọ pẹlu; a ki yio fi ibósẹ-ẹran kan silẹ lẹhin; nitori ninu rẹ̀ li awa o mú sìn OLUWA Ọlọrun wa; awa kò si mọ̀ ohun na ti a o fi sìn OLUWA, titi awa o fi dé ibẹ̀. 27 Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, kò si fẹ́ jẹ ki nwọn lọ. 28 Farao si wi fun u pe, Kuro lọdọ mi, ma ṣọ́ ara rẹ, máṣe tun ri oju mi mọ́; nitori ni ijọ́ na ti iwọ ba ri oju mi iwọ o kú. 29 Mose si wipe, Iwọ fọ̀ rere; emi ki yio tun ri oju rẹ mọ́.

Eksodu 11

Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o tun mú iyọnu kan wá sara Farao, ati sara Egipti; lẹhin eyinì ni on o jọwọ nyin lọwọ lọ lati ihin: nigbati on o jẹ ki ẹ lọ, àtitán ni yio tì nyin jade nihin. 2 Wi nisisiyi li eti awọn enia wọnyi, ki olukuluku ọkunrin ki o bère lọdọ aladugbo rẹ̀ ati olukuluku obinrin lọdọ aladugbo rẹ̀, ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà. 3 OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na. 4 Mose si wipe, Bayi li OLUWA wi, Lãrin ọganjọ li emi o jade lọ sãrin Egipti: 5 Gbogbo awọn akọ́bi ti o wà ni ilẹ Egipti ni yio si kú, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀, titi yio si fi dé akọ́bi iranṣẹbinrin ti o wà lẹhin ọlọ; ati gbogbo akọ́bi ẹran. 6 Ẹkún nla yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, eyiti irú rẹ̀ kò si ri, ti ki yio si si irú rẹ̀ mọ́. 7 Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli. 8 Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla. 9 OLUWA si wi fun Mose pe, Farao ki yio gbọ́ tirẹ; ki a le sọ iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. 10 Mose ati Aaroni si ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu wọnyi niwaju Farao: OLUWA si mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si fẹ́ jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o jade lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.

Eksodu 12

Àjọ Ìrékọjá

1 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni ni ilẹ Egipti pe, 2 Oṣù yi ni yio ṣe akọ́kà oṣù fun nyin: on ni yio ṣe ekini oṣù ọdún fun nyin. 3 Ẹ sọ fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli pe, Ni ijọ́ kẹwa oṣù yi ni ki olukuluku wọn ki o mú ọdọ-agutan sọdọ, gẹgẹ bi ile baba wọn, ọdọ-agutan kan fun ile kan: 4 Bi awọn ara ile na ba si kere jù ìwọn ọdọ-agutan na lọ, ki on ati aladugbo rẹ̀ ti o sunmọ-eti ile rẹ̀, ki o mú gẹgẹ bi iye awọn ọkàn na, olukuluku ni ìwọn ijẹ rẹ̀ ni ki ẹ ṣiro ọdọ-agutan na. 5 Ailabùku ni ki ọdọ-agutan nyin ki o jẹ́, akọ ọlọdún kan: ẹnyin o mú u ninu agutan, tabi ninu ewurẹ: 6 Ẹnyin o si fi i pamọ́ titi o fi di ijọ́ kẹrinla oṣù na: gbogbo agbajọ ijọ Israeli ni yio pa a li aṣalẹ. 7 Nwọn o si mú ninu ẹ̀jẹ na, nwọn o si fi tọ́ ara opó ìha mejeji, ati sara atẹrigba ile wọnni, ninu eyiti nwọn o jẹ ẹ. 8 Nwọn o si jẹ ẹran na ti a fi iná sun li oru na, ati àkara alaiwu; ewebẹ kikorò ni nwọn o fi jẹ ẹ. 9 Ẹ máṣe jẹ ninu rẹ̀ ni tutù, tabi ti a fi omi bọ̀, bikoṣepe sisun ninu iná; ati ori rẹ̀, ati itan rẹ̀, ati akopọ̀ inu rẹ̀ pẹlu. 10 Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun. 11 Bayi li ẹnyin o si jẹ ẹ; ti ẹnyin ti àmure didì li ẹgbẹ nyin, bàta nyin li ẹsẹ̀ nyin, ati ọpá nyin li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si yara jẹ ẹ: irekọja OLUWA ni. 12 Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA. 13 Ẹ̀jẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹ̀jẹ na, emi o ré nyin kọja, iyọnu na ki yio wá sori nyin lati run nyin nigbati mo ba kọlù ilẹ Egipti. 14 Ọjọ́ oni ni yio si ma ṣe ọjọ́ iranti fun nyin, ẹnyin o si ma ṣe e li ajọ fun OLUWA ni iran-iran nyin, ẹ o si ma ṣe e li ajọ nipa ìlana lailai.

Àjọ̀dún Àìwúkàrà

15 Ijọ́ meje li ẹ o fi ma jẹ àkara alaiwu; li ọjọ́ kini gan li ẹ o palẹ iwukàra mọ́ kuro ni ile nyin; nitori ẹniti o ba jẹ àkara wiwu lati ọjọ́ kini lọ titi o fi di ọjọ́ keje, ọkàn na li a o ke kuro ninu Israeli. 16 Ati li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà, ati li ọjọ́ keje apejọ mimọ́ yio wà fun nyin; a ki yio ṣe iṣẹkiṣẹ ninu wọn, bikoṣe eyiti olukuluku yio jẹ, kìki eyinì li a le ṣe ninu nyin. 17 Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai. 18 Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ. 19 Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na. 20 Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.

Àjọ Ìrékọjá Kinni

21 Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na. 22 Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀. 23 Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin. 24 Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai. 25 O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi. 26 Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi? 27 Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn. 28 Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.

Ikú Àwọn Àkọ́bí

29 O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin. 30 Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú. 31 O si pè Mose on Aaroni li oru, o si wipe, Ẹ dide, ki ẹ jade lọ kuro lãrin awọn enia mi, ati ẹnyin ati awọn ọmọ Israeli; ki ẹ si lọ sìn OLUWA, bi ẹ ti wi. 32 Ẹ si mú agbo nyin ati ọwọ́-ẹran nyin, bi ẹ ti wi, ki ẹ si ma lọ; ki ẹ si sure fun mi pẹlu. 33 Awọn ara Egipti si nrọ̀ awọn enia na, ki nwọn ki o le rán wọn jade lọ kuro ni ilẹ na kánkan; nitoriti nwọn wipe, Gbogbo wa di okú. 34 Awọn enia na si mú iyẹfun pipò wọn ki nwọn ki o to fi iwukàra si i, a si dì ọpọ́n ìpo-iyẹfun wọn sinu aṣọ wọn lé ejika wọn. 35 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; nwọn si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ lọwọ awọn ara Egipti. 36 OLUWA si fun awọn enia na li ojurere li oju awọn ara Egipti, bẹ̃ni nwọn si fun wọn li ohun ti nwọn bère. Nwọn si kó ẹrù awọn ara Egipti. 37 Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde. 38 Ati ọ̀pọ enia ti o dàpọ mọ́ wọn bá wọn goke lọ pẹlu; ati agbo, ati ọwọ́-ẹran, ani ọ̀pọlọpọ ẹran. 39 Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn. 40 Njẹ ìgba atipo awọn ọmọ Israeli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti, o jẹ́ irinwo ọdún o le ọgbọ̀n. 41 O si ṣe li opin irinwo ọdún o le ọgbọ̀n, ani li ọjọ́ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun OLUWA jade kuro ni ilẹ Egipti. 42 Oru ti a ikiyesi ni gidigidi si OLUWA ni mimú wọn jade kuro ni ilẹ Egipti: eyi li oru ti a ikiyesi si OLUWA, li ati irandiran gbogbo awọn ọmọ Israeli. 43 OLUWA si wi fun Mose ati Aaroni pe, Eyi ni ìlana irekọja: alejokalejò ki yio jẹ ninu rẹ̀: 44 Ṣugbọn iranṣẹ ẹnikẹni ti a fi owo rà, nigbati iwọ ba kọ ọ nilà, nigbana ni ki o jẹ ninu rẹ̀. 45 Alejò ati alagbaṣe ki yio jẹ ninu rẹ̀. 46 Ni ile kan li a o jẹ ẹ; iwọ kò gbọdọ mú ninu ẹran rẹ̀ jade sode kuro ninu ile na; bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọ́ ọkan ninu egungun rẹ̀. 47 Gbogbo ijọ Israeli ni yio ṣe e. 48 Nigbati alejò kan ba nṣe atipo lọdọ rẹ, ti o si nṣe ajọ irekọja si OLUWA, ki a kọ gbogbo ọkunrin rẹ̀ nilà, nigbana ni ki ẹ jẹ ki o sunmọtosi, ki o si ṣe e; on o si dabi ẹniti a bi ni ilẹ na: nitoriti kò si ẹni alaikọlà ti yio jẹ ninu rẹ̀. 49 Ofin kan ni fun ibilẹ ati fun alejò ti o ṣe atipo ninu nyin. 50 Bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ṣe; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe. 51 O si ṣe li ọjọ́ na gan, OLUWA mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.

Eksodu 13

1 OLUWA si wi fun Mose pe, 2 Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe. 3 Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ ranti ọjọ́ oni, ninu eyiti ẹnyin jade kuro ni Egipti, kuro li oko-ẹrú; nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú nyin jade kuro nihin: a ki yio si jẹ àkara wiwu. 4 Li ọjọ́ oni li ẹnyin jade li oṣù Abibu. 5 Yio si ṣe nigbati OLUWA yio mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn enia Hitti, ati ti awọn ara Amori, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, on ni iwọ o ma sìn ìsin yi li oṣù yi. 6 Ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, li ọjọ́ keje li ajọ yio wà fun OLUWA. 7 Ọjọ́ meje li a o fi jẹ àkara alaiwu; ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ, bẹ̃ni ki a má si ṣe ri iwukàra lọdọ rẹ ni gbogbo ẹkùn rẹ. 8 Iwọ o si sọ fun ọmọ rẹ li ọjọ́ na pe, A nṣe eyi nitori eyiti OLUWA ṣe fun mi nigbati mo jade kuro ni Egipti. 9 Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti. 10 Nitorina ni ki iwọ ki o ma kiyesi ìlana yi li akokò rẹ̀ li ọdọdún. 11 Yio si ṣe nigbati OLUWA ba mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, bi o ti bura fun ọ, ati fun awọn baba rẹ, ti yio si fi fun ọ. 12 Ni iwọ o si yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun OLUWA, ati gbogbo akọ́bi ẹran ti iwọ ni; ti OLUWA li awọn akọ. 13 Ati gbogbo akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada; bi iwọ kò ba rà a pada, njẹ ki iwọ ki o sẹ ẹ li ọrùn: ati gbogbo akọ́bi enia ninu awọn ọmọ ọkunrin rẹ ni iwọ o rapada. 14 Yio si ṣe nigbati ọmọ rẹ yio bère lọwọ rẹ lẹhin-ọla pe, Kili eyi? ki iwọ ki o wi fun u pe, Ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni ilẹ Egipti, kuro li oko-ẹrú: 15 O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada. 16 Yio si ma ṣe àmi li ọwọ́ rẹ, ati ọjá-igbaju lagbedemeji oju rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni Egipti. 17 O si ṣe, nigbati Farao jẹ ki awọn enia na ki o lọ tán, Ọlọrun kò si mú wọn tọ̀ ọ̀na ilẹ awọn ara Filistia, eyi li o sa yá; nitoriti Ọlọrun wipe, Ki awọn enia má ba yi ọkàn pada nigbati nwọn ba ri ogun, ki nwọn si pada lọ si Egipti. 18 Ṣugbọn Ọlọrun mu wọn yi lọ li ọ̀na ijù Okun Pupa: awọn ọmọ Israeli jade lọ kuro ni ilẹ Egipti ni ihamọra. 19 Mose si gbé egungun Josefu lọ pẹlu rẹ̀; nitori ibura lile li o mu awọn ọmọ Israeli bu pe, Lõtọ li Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò; ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lọ pẹlu nyin kuro nihin. 20 Nwọn si mu ọ̀na-àjo wọn pọ̀n lati Sukkoti lọ, nwọn si dó si Etamu leti ijù. 21 OLUWA si nlọ niwaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma li ọsán, lati ma ṣe amọna fun wọn; ati li oru li ọwọ̀n iná lati ma fi imọlẹ fun wọn; lati ma rìn li ọsán ati li oru. 22 Ọwọ̀n awọsanma na kò kuro li ọsán, tabi ọwọ̀n iná li oru, niwaju awọn enia na.

Eksodu 14

1 OLUWA si wi fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o dari, ki nwọn ki o si dó si iwaju Pi-hahirotu, li agbedemeji Migdolu on okun, niwaju Baal-sefoni: lọkankan rẹ̀ li ẹba okun ni ki ẹnyin ki o dó si. 3 Nitoriti Farao yio wi niti awọn ọmọ Israeli pe, Nwọn há ni ilẹ na, ijù na sé wọn mọ́. 4 Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃. 5 A si wi fun ọba Egipti pe, awọn enia na sá: àiya Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀ si yi si awọn enia na, nwọn si wipe, Ẽṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu ìsin wa? 6 O si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si mú awọn enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 7 O si mú ẹgbẹta ãyo kẹkẹ́, ati gbogbo kẹkẹ́ Egipti, ati olori si olukuluku wọn. 8 OLUWA si mu àiya Farao ọba Egipti le, o si lepa awọn ọmọ Israeli: ọwọ́ giga li awọn ọmọ Israeli si fi jade lọ. 9 Ṣugbọn awọn ara Egipti lepa wọn, gbogbo ẹṣin ati kẹkẹ́ Farao, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, ati awọn ogun rẹ̀, o si lé wọn bá, nwọn duro li ẹba okun ni ìha Pi-hahirotu niwaju Baal-sefoni. 10 Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA. 11 Nwọn si wi fun Mose pe, Nitoriti isà kò sí ni Egipti, ki iwọ ṣe mú wa wá lati kú ni ijù? ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃, lati mú wa jade ti Egipti wá? 12 Ọrọ yi ki awa ti sọ fun ọ ni Egipti pe, Jọwọ wa jẹ ki awa ki o ma sìn awọn ara Egipti? O sá san fun wa lati ma sin awọn ara Egipti, jù ki awa kú li aginjù lọ. 13 Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai. 14 Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́. 15 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkepè mi? sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o tẹ̀ siwaju: 16 Ṣugbọn iwọ gbé ọpá rẹ soke, ki iwọ ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju okun ki o si yà a meji: awọn ọmọ Israeli yio si là ãrin okun na kọja ni iyangbẹ ilẹ. 17 Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 18 Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba gbà ogo lori Farao, lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 19 Angeli Ọlọrun na ti o ṣaju ogun Israeli, o si ṣi lọ ṣẹhin wọn; ọwọ̀n awọsanma si ṣi kuro niwaju wọn, o si duro lẹhin wọn: 20 O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na. 21 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun; OLUWA si fi afẹfẹ lile ìla-õrùn mu okun bì sẹhin ni gbogbo oru na, o si mu okun gbẹ: omi na si pinya. 22 Awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ãrin okun ni ilẹ gbigbẹ: omi si ṣe odi si wọn li ọwọ ọtún, ati ọwọ́ òsi. 23 Awọn ara Egipti si lepa wọn, nwọn si wọ̀ ọ tọ̀ wọn lọ lãrin okun, ati gbogbo ẹṣin Farao, ati kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 24 O si ṣe, nigba iṣọ owurọ̀, OLUWA bojuwò ogun ara Egipti lãrin ọwọ̀n iná, ati ti awọsanma, o si pá ogun awọn ara Egipti làiya. 25 O si yẹ̀ kẹkẹ́ wọn, nwọn si nwọ́ turu, awọn ara Egipti si wipe, Ẹ jẹ ki a sá kuro niwaju Israeli; nitoriti OLUWA mbá awọn ara Egipti jà fun wọn. 26 OLUWA si wi fun Mose pe; Nà ọwọ́ rẹ si oju okun, ki omi ki o tun pada wá sori awọn ara Egipti, sori kẹkẹ́ wọn, ati sori ẹlẹṣin wọn. 27 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun, okun si pada bọ̀ si ipò rẹ̀ nigbati ilẹ mọ́; awọn ara Egipti si sá lù u. OLUWA si bì awọn ara Egipti ṣubu lãrin okun. 28 Omi si pada, o si bò kẹkẹ́, ati awọn ẹlẹṣin, ati gbogbo ogun Farao ti o wọ̀ inu okun tọ̀ wọn lẹhin lọ; ọkanṣoṣo kò kù ninu wọn. 29 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni iyangbẹ ilẹ lãrin okun; omi si jẹ́ odi fun wọn li ọwọ́ ọtún, ati li ọwọ́ òsi wọn. 30 Bayi li OLUWA gbà Israeli là li ọjọ́ na lọwọ awọn ara Egipti; Israeli si ri okú awọn ara Egipti leti okun. 31 Israeli si ri iṣẹ nla ti OLUWA ṣe lara awọn ara Egipti: awọn enia na si bẹ̀ru OLUWA, nwọn si gbà OLUWA ati Mose iranṣẹ rẹ̀ gbọ́.

Eksodu 15

1 NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. 2 OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke. 3 Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀. 4 Kẹkẹ́ Farao ati ogun rẹ̀ li o mu wọ̀ inu okun: awọn ãyo olori ogun rẹ̀ li o si rì ninu Okun Pupa. 5 Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta. 6 OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ li ogo ninu agbara: OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ fọ́ ọtá tútu. 7 Ati ni ọ̀pọlọpọ ọlá rẹ ni iwọ bì awọn ti o dide si ọ ṣubu; iwọ rán ibinu rẹ, ti o run wọn bi akemọlẹ idi koriko. 8 Ati nipa ẽmi imu rẹ, li omi si fi wọjọ pọ̀, ìṣan omi dide duro gangan bi ogiri; ibú si dìlu lãrin okun. 9 Ọtá wipe, Emi o lepa, emi o bá wọn, emi o pín ikogun: a o tẹ́ ifẹkufẹ mi lọrùn lara wọn; emi o fà dà mi yọ, ọwọ́ mi ni yio pa wọn run. 10 Iwọ si mu afẹfẹ rẹ fẹ́, okun bò wọn mọlẹ: nwọn rì bi ojé ninu omi nla. 11 Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ́, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu? 12 Iwọ nà ọwọ́ ọtún rẹ, ilẹ gbe wọn mì. 13 Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ. 14 Awọn enia gbọ́, nwọn warìri; ikãnu si mú awọn olugbe Palestina. 15 Nigbana li ẹnu yà awọn balẹ Edomu; iwarìri si mú awọn alagbara Moabu: gbogbo awọn olugbe Kenaani yọ́ dànu. 16 Ibẹru-bojo mú wọn; nipa titobi apa rẹ nwọn duro jẹ bi okuta; titi awọn enia rẹ fi rekọja, OLUWA, titi awọn enia rẹ ti iwọ ti rà fi rekọja. 17 Iwọ o mú wọn wọle, iwọ o si gbìn wọn sinu oke ilẹ-iní rẹ, OLUWA, ni ibi ti iwọ ti ṣe fun ara rẹ, lati mã gbé, OLUWA; ni ibi mimọ́ na, ti ọwọ́ rẹ ti gbekalẹ. 18 OLUWA yio jọba lai ati lailai. 19 Nitori ẹṣin Farao wọ̀ inu okun lọ, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, OLUWA si tun mú omi okun pada si wọn lori; ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni ilẹ gbigbẹ lãrin okun. 20 Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó. 21 Miriamu si da wọn li ohùn pe, Ẹ kọrin si OLUWA nitoriti o pọ̀ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. 22 Bẹ̃ni Mose mú Israeli jade lati Okun Pupa wá, nwọn si jade lọ si ijù Ṣuri; nwọn si lọ ni ìrin ijọ́ mẹta ni ijù na, nwọn kò si ri omi. 23 Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara. 24 Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu? 25 O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò; 26 O si wipe, Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ́ li oju rẹ̀, ti iwọ o ba si fetisi ofin rẹ̀, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá. 27 Nwọn si dé Elimu, nibiti kanga omi mejila gbé wà, ati ãdọrin ọpẹ: nwọn si dó si ìha omi wọnni nibẹ̀.

Eksodu 16

1 NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti. 2 Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na: 3 Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi. 4 Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ. 5 Yio si ṣe, li ọjọ́ kẹfa, nwọn o si pèse eyiti nwọn múwa; yio si to ìwọn meji eyiti nwọn ima kó li ojojumọ́. 6 Mose ati Aaroni si wi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli pe, Li aṣalẹ, li ẹnyin o si mọ̀ pe, OLUWA li o mú nyin jade lati Egipti wá: 7 Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa? 8 Mose si wi pe, Bayi ni yio ri nigbati OLUWA yio fun nyin li ẹran jẹ li aṣalẹ, ati onjẹ ajẹyo li owurọ̀; nitoriti OLUWA gbọ́ kikùn nyin ti ẹnyin kùn si i: ta si li awa? kikùn nyin ki iṣe si wa, bikoṣe si OLUWA. 9 Mose si sọ fun Aaroni pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ iwaju OLUWA, nitoriti o ti gbọ́ kikùn nyin. 10 O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na. 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli: sọ fun wọn pe, Li aṣalẹ ẹnyin o jẹ ẹran, ati li owurọ̀ a o si fi onjẹ kún nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 13 O si ṣe li aṣalẹ ni aparò fò dé, nwọn si bò ibudó mọlẹ; ati li owurọ̀ ìri si sẹ̀ yi gbogbo ibudó na ká. 14 Nigbati ìri ti o sẹ̀ bolẹ si fà soke, si kiyesi i, lori ilẹ ijù na, ohun ribiribi, o kere bi ìri didì li ori ilẹ. 15 Nigbati awọn ọmọ Israeli si ri i, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili eyi? nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun na. Mose si wi fun wọn pe, Eyi li onjẹ ti OLUWA fi fun nyin lati jẹ. 16 Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, ki olukuluku ki o ma kó bi ìwọn ijẹ rẹ̀; òṣuwọn omeri kan fun ẹni kọkan, gẹgẹ bi iye awọn enia nyin, ki olukuluku nyin mú fun awọn ti o wà ninu agọ́ rẹ̀. 17 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si kó, ẹlomiran pupọ̀jù, ẹlomiran li aito. 18 Nigbati nwọn si fi òṣuwọn omeri wọ̀n ọ, ẹniti o kó pupọ̀ kò ni nkan lé, ẹniti o si kó kere jù, kò ṣe alaito nwọn si kó olukuluku bi ijẹ tirẹ̀. 19 Mose si wi fun wọn pe, Ki ẹnikan ki o má kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀. 20 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ti Mose; bẹ̃li ẹlomiran si kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, o si di idin, o si rùn; Mose si binu si wọn. 21 Nwọn si nkó o li orowurọ̀, olukuluku bi ijẹ tirẹ̀; nigbati õrùn si mu, o yọ́. 22 O si ṣe ni ijọ́ kẹfa, nwọn kó ìwọn onjẹ ẹrinmeji, omeri meji fun ẹni kọkan: gbogbo awọn olori ijọ na si wá nwọn sọ fun Mose. 23 O si wi fun wọn pe, Eyi na li OLUWA ti wi pe, Ọla li ọjọ́ isimi, isimi mimọ́ fun OLUWA; ẹ yan eyiti ẹnyin ni iyan, ki ẹ si bọ̀ eyiti ẹnyin ni ibọ̀; eyiti o si kù, ẹ fi i silẹ lati pa a mọ́ dé owurọ̀. 24 Nwọn si fi i silẹ titi di owurọ̀, bi Mose ti paṣẹ fun wọn; kò si rùn, bẹ̃ni kò sí idin ninu rẹ̀. 25 Mose si wi pe, Ẹ jẹ eyinì li oni; nitori oni li ọjọ́ isimi fun OLUWA: li oni ẹnyin ki yio ri i ninu igbẹ́. 26 Li ọjọ́ mẹfa li ẹ o ma kó o; ṣugbọn li ọjọ́ keje li ọjọ́ isimi, ninu rẹ̀ ni ki yio si nkan. 27 O si ṣe li ọjọ́ keje awọn kan ninu awọn enia jade lọ ikó, nwọn kò si ri nkan. 28 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹ o ti kọ̀ lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́ pẹ to? 29 Wò o, OLUWA sa ti fi ọjọ́ isimi fun nyin, nitorina li o ṣe fi onjẹ ijọ́ meji fun nyin li ọjọ́ kẹfa; ki olukuluku ki o joko ni ipò rẹ̀, ki ẹnikẹni ki o máṣe jade kuro ni ipò rẹ̀ li ọjọ́ keje. 30 Bẹ̃li awọn enia na simi li ọjọ́ keje. 31 Awọn ara ile Israeli si pè orukọ rẹ̀ ni Manna; o si dabi irugbìn korianderi, funfun; adùn rẹ̀ si dabi àkara fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe. 32 Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, Ẹ kún òṣuwọn omeri kan ninu rẹ̀ lati pamọ́ fun irandiran nyin; ki nwọn ki o le ma ri onjẹ ti mo fi bọ́ nyin ni ijù, nigbati mo mú nyin jade kuro ni ilẹ Egipti 33 Mose si wi fun Aaroni pe, Mú ìkoko kan, ki o si fi òṣuwọn omeri kan ti o kún fun manna sinu rẹ̀, ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA, lati pa a mọ́ fun irandiran nyin. 34 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li Aaroni gbé e kalẹ niwaju ibi Ẹrí lati pa a mọ́. 35 Awọn ọmọ Israeli si jẹ manna li ogoji ọdún, titi nwọn fi dé ilẹ ti a tẹ̀dó; nwọn jẹ manna titi nwọn fi dé àgbegbe ilẹ Kenaani. 36 Njẹ òṣuwọn omeri kan ni idamẹwa efa.

Eksodu 17

1 GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si rìn lati ijù Sini lọ, ni ìrin wọn, gẹgẹ bi ofin OLUWA, nwọn si dó ni Refidimu: omi kò si si fun awọn enia na lati mu. 2 Nitorina li awọn enia na ṣe mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Fun wa li omi ki a mu. Mose si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbà mi sọ̀? ẽṣe ti ẹnyin fi ndán OLUWA wò? 3 Ongbẹ omi si ngbẹ awọn enia na nibẹ̀; awọn enia na si nkùn si Mose, nwọn si wipe, Ẽtiri ti iwọ fi mú wa goke lati Egipti wá, lati fi ongbẹ pa wa ati awọn ọmọ wa, ati ẹran wa? 4 Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta. 5 OLUWA si wi fun Mose pe, Kọja lọ siwaju awọn enia na, ki o si mú ninu awọn àgbagba Israeli pẹlu rẹ, ki o si mú ọpá rẹ, ti o fi lù odò nì li ọwọ́ rẹ, ki o si ma lọ. 6 Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli. 7 O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si? 8 Nigbana li Amaleki wá, o si bá Israeli jà ni Refidimu. 9 Mose si wi fun Joṣua pe, Yàn enia fun wa, ki o si jade lọ ibá Amaleki jà: li ọla li emi o duro lori oke ti emi ti ọpá Ọlọrun li ọwọ́ mi. 10 Joṣua si ṣe bi Mose ti wi fun u, o si bá Amaleki jà: ati Mose, Aaroni, on Huri lọ sori oke na. 11 O si ṣe, nigbati Mose ba gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, Israeli a bori: nigbati o ba si rẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ silẹ, Amaleki a bori. 12 Ṣugbọn ọwọ́ kún Mose; nwọn si mú okuta kan, nwọn si fi si abẹ rẹ̀, o si joko lé e; Aaroni ati Huri si mu u li ọwọ́ ró, ọkan li apa kini, ekeji li apa keji; ọwọ́ rẹ̀ si duro gan titi o fi di ìwọ-õrùn. 13 Joṣua si fi oju idà ṣẹgun Amaleki ati awọn enia rẹ̀ tútu 14 OLUWA si wi fun Mose pe, Kọ eyi sinu iwe fun iranti, ki o si kà a li eti Joṣua; nitoriti emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun. 15 Mose si tẹ́ pẹpẹ kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni JEHOFA-nissi: 16 O si wipe, OLUWA ti bura: OLUWA yio bá Amaleki jà lati irandiran.

Eksodu 18

1 NIGBATI Jetro, alufa Midiani, ana Mose, gbọ́ ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun Mose, ati fun Israeli awọn enia rẹ̀, ati pe, OLUWA mú Israeli lati Egipti jade wá; 2 Nigbana ni Jetro, ana Mose, mú Sippora aya Mose wá, lẹhin ti o ti rán a pada. 3 Ati awọn ọmọ rẹ̀ mejeji: ti orukọ ọkan njẹ Gerṣomu; nitoriti o wipe, Emi ṣe alejò ni ilẹ ajeji. 4 Ati orukọ ekeji ni Elieseri; nitoriti o wipe, Ọlọrun baba mi li alatilẹhin mi, o si gbà mi lọwọ idà Farao: 5 Ati Jetro, ana Mose, o tọ̀ Mose wá ti on ti awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀ si ijù, nibiti o gbé dó si lẹba oke Ọlọrun. 6 O si wi fun Mose pe, Emi Jetro ana rẹ li o tọ̀ ọ wá, pẹlu aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ̀. 7 Mose si jade lọ ipade ana rẹ̀, o si tẹriba, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, nwọn si bére alafia ara wọn; nwọn si wọ̀ inu agọ́. 8 Mose si sọ ohun gbogbo ti OLUWA ti ṣe si Farao, ati si awọn ara Egipti nitori Israeli fun ana rẹ̀, ati gbogbo ipọnju ti o bá wọn li ọ̀na, ati bi OLUWA ti gbà wọn. 9 Jetro si yọ̀ nitori gbogbo ore ti OLUWA ti ṣe fun Israeli, ẹniti o ti gbàla lọwọ awọn ara Egipti. 10 Jetro si wipe, Olubukún li OLUWA, ẹniti o gbà nyin là lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ Farao, ẹniti o gbà awọn enia là lọwọ awọn ara Egipti. 11 Mo mọ̀ nisisiyi pe OLUWA tobi jù gbogbo oriṣa lọ: nitõtọ, ninu ọ̀ran ti nwọn ti ṣeféfe si wọn. 12 Jetro, ana Mose, si mù ẹbọ sisun, ati ẹbọ wá fun Ọlọrun: Aaroni si wá, ati gbogbo awọn àgba Israeli, lati bá ana Mose jẹun niwaju Ọlọrun. 13 O si ṣe ni ijọ́ keji ni Mose joko lati ma ṣe idajọ awọn enia: awọn enia si duro tì Mose lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ. 14 Nigbati ana Mose si ri gbogbo eyiti on nṣe fun awọn enia, o ni, Kili eyiti iwọ nṣe fun awọn enia yi? ẽṣe ti iwọ nikan fi dá joko, ti gbogbo enia si duro tì ọ, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ? 15 Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni: 16 Nigbati nwọn ba li ẹjọ́, nwọn a tọ̀ mi wá; emi a si ṣe idajọ larin ẹnikini ati ẹnikeji, emi a si ma mú wọn mọ̀ ìlana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀. 17 Ana Mose si wi fun u pe, Eyiti iwọ nṣe nì kò dara. 18 Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn enia yi ti o pẹlu rẹ: nitoriti nkan yi wuwo jù fun ọ; iwọ nikan ki yio le ṣe e tikalãrẹ. 19 Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun. 20 Ki o si ma kọ́ wọn ni ìlana ati ofin wọnni, ki o si ma fi ọ̀na ti nwọn o ma rìn hàn fun wọn ati iṣẹ ti nwọn o ma ṣe. 21 Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa. 22 Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na. 23 Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia. 24 Mose si gbà ohùn ana rẹ̀ gbọ́, o si ṣe ohun gbogbo ti o wi. 25 Mose si yàn awọn enia ti o to ninu gbogbo Israeli, o si fi wọn ṣe olori awọn enia, olori ẹgbẹgbẹrun, olori ọrọrún, olori arãdọta, olori mẹwamẹwa. 26 Nwọn si nṣe idajọ awọn enia nigbakugba: ọ̀ran ti o ṣoro, nwọn a mútọ̀ Mose wá, ṣugbọn awọn tikalawọn ṣe idajọ gbogbo ọ̀ran kekeké. 27 Mose si jẹ ki ana rẹ̀ ki o lọ; on si ba tirẹ̀ lọ si ilẹ rẹ̀.

Eksodu 19

1 LI oṣù kẹta, ti awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti tán, li ọjọ́ na gan ni nwọn dé ijù Sinai. 2 Nwọn sá ti ṣi kuro ni Refidimu, nwọn si wá si ijù Sinai, nwọn si dó si ijù na; nibẹ̀ ni Israeli si dó si niwaju oke na. 3 Mose si goke tọ̀ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakobu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israeli pe; 4 Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-ìyẹ́ idì, ti mo si mú nyin tọ̀ ara mi wá. 5 Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ́ gbà ohùn mi gbọ́ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ́, nigbana li ẹnyin o jẹ́ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. 6 Ẹnyin o si ma jẹ́ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ́. Wọnyi li ọ̀rọ ti iwọ o sọ fun awọn ọmọ Israeli. 7 Mose si wá o si ranṣẹ pè awọn àgba awọn enia, o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi lelẹ niwaju wọn ti OLUWA palaṣẹ fun u. 8 Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọ̀rọ awọn enia pada tọ̀ OLUWA lọ. 9 OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi tọ̀ ọ wá ninu awọsanma ṣíṣu, ki awọn enia ki o le ma gbọ́ nigbati mo ba mbá ọ sọ̀rọ, ki nwọn ki o si ma gbà ọ gbọ́ pẹlu lailai. Mose si sọ ọ̀rọ awọn enia na fun OLUWA. 10 OLUWA si wi fun Mose pe, Tọ̀ awọn enia yi lọ, ki o si yà wọn simimọ́ li oni ati li ọla, ki nwọn ki o si fọ̀ asọ wọn. 11 Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo. 12 Ki iwọ ki o si sagbàra fun awọn enia yiká, pe, Ẹ ma kiyesi ara nyin, ki ẹ máṣe gùn ori oke lọ, ki ẹ má si ṣe fọwọbà eti rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn oke na, pipa ni nitõtọ: 13 Ọwọkọwọ́ kò gbọdọ kàn a, bikoṣepe ki a sọ ọ li okuta, tabi ki a gún u pa nitõtọ; iba ṣe ẹranko iba ṣe enia, ki yio là a: nigbati ipè ba dún, ki nwọn ki o gùn oke wá. 14 Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn. 15 O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin. 16 O si ṣe, li owurọ̀ ijọ́ kẹta, ni ãrá ati mànamána wà, ati awọsanma ṣíṣu dùdu lori òke na, ati ohùn ipè na si ndún kikankikan; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti o wà ni ibudó warìri. 17 Mose si mú awọn enia jade lati ibudó wá lati bá Ọlọrun pade; nwọn si duro ni ìha isalẹ oke na. 18 Oke Sinai si jẹ́ kìki ẽfi, nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rẹ̀ ninu iná: ẽfi na si goke bi ẽfi ileru, gbogbo oke na si mì tìtì. 19 O si ṣe ti ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji, Mose sọ̀rọ, Ọlọrun si fi ãrá da a li ohùn. 20 OLUWA si sọkalẹ wá si oke Sinai, lori oke na: OLUWA si pè Mose lori oke na; Mose si goke lọ. 21 OLUWA si wi fun Mose pe, Sọkalẹ, kìlọ fun awọn enia, ki nwọn ki o má ba yà sọdọ OLUWA lati bẹ̀ ẹ wò, ki ọ̀pọ ki o má ba ṣegbe ninu wọn. 22 Si jẹ ki awọn alufa pẹlu, ti o sunmọ OLUWA, ki o yà ara wọn si mimọ́, ki OLUWA ki o má ba kọlù wọn. 23 Mose si wi fun OLUWA pe, Awọn enia ki yio le wá sori oke Sinai: nitoriti iwọ ti kìlọ fun wa pe, Sọ agbàra yi oke na ká, ki o si yà a si mimọ́. 24 OLUWA si wi fun u pe, Lọ, sọkalẹ; ki iwọ ki o si goke wá, iwọ ati Aaroni pẹlu rẹ: ṣugbọn ki awọn alufa ati awọn enia ki o máṣe yà lati goke tọ̀ OLUWA wá, ki o má ba kọlù wọn. 25 Bẹ̃ni Mose sọkalẹ tọ̀ awọn enia lọ, o si sọ̀rọ fun wọn.

Eksodu 20

1 ỌLỌRUN si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi pe, 2 Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. 3 Iwọ kò gbọdọ lí Ọlọrun miran pẹlu mi. 4 Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ. 5 Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi; 6 Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́. 7 Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn. 8 Ranti ọjọ́ isimi, lati yà a simimọ́. 9 Ọjọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: 10 Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ: 11 Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́. 12 Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 13 Iwọ kò gbọdọ pania. 14 Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. 15 Iwọ kò gbọdọ jale. 16 Iwọ kò gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ. 17 Iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, tabi ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ. 18 Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére. 19 Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú. 20 Mose si wi fun awọn enia pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitoriti Ọlọrun wá lati dan nyin wò, ati ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o le ma wà li oju nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀. 21 Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà. 22 OLUWA si wi fun Mose pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti bá nyin sọ̀rọ lati ọrun wá. 23 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wurà, fun ara nyin. 24 Pẹpẹ erupẹ ni ki iwọ mọ fun mi, lori rẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, ati ẹbọ alafia rẹ, agutan rẹ, ati akọmalu rẹ: ni ibi gbogbo ti mo ba gbé fi iranti orukọ mi si, emi o ma tọ̀ ọ wá, emi o si ma bukún fun ọ. 25 Bi iwọ o ba si mọ pẹpẹ okuta fun mi, iwọ kò gbọdọ fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: nitori bi iwọ ba gbé ohun-ọnà rẹ lé ori rẹ̀, iwọ sọ ọ di aimọ́. 26 Iwọ kò si gbọdọ ba àkasọ gùn ori pẹpẹ mi, ki ìhoho rẹ ki o máṣe hàn lori rẹ̀.

Eksodu 21

1 NJẸ wọnyi ni idajọ ti iwọ o gbekalẹ niwaju wọn. 2 Bi iwọ ba rà ọkunrin Heberu li ẹrú, ọdún mẹfa ni on o sìn: li ọdún keje yio si jade bi omnira lọfẹ. 3 Bi o ba nikan wọle wá, on o si nikan jade lọ: bi o ba ti gbé iyawo, njẹ ki aya rẹ̀ ki o bá a jade lọ. 4 Bi o ba ṣepe oluwa rẹ̀ li o fun u li aya, ti on si bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin fun u; aya ati awọn ọmọ ni yio jẹ́ ti oluwa rẹ̀, on tikara rẹ̀ yio si nikan jade lọ. 5 Bi ẹru na ba si wi ni gbangba pe, Emi fẹ́ oluwa mi, aya mi, ati awọn ọmọ mi; emi ki yio jade lọ idi omnira: 6 Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye. 7 Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ. 8 Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ. 9 Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni. 10 Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀. 11 Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo. 12 Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a. 13 Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si. 14 Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú. 15 Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a. 16 Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a. 17 Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a. 18 Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ: 19 Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa. 20 Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ. 21 Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe. 22 Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ. 23 Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipò ẹmi. 24 Fi oju dipò oju, ehín dipò ehín, ọwọ́ dipò ọwọ́, ẹsẹ̀ dipò ẹsẹ̀. 25 Fi ijóna dipò ijóna, ọgbẹ́, dipò ọgbẹ́, ìna dipò ìna. 26 Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀. 27 Bi o ba si ká ehín ẹrú rẹ̀ ọkunrin, tabi ehín ẹrú rẹ̀ obinrin; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori ehín rẹ̀. 28 Bi akọmalu ba kàn ọkunrin tabi obinrin ti o si kú: sísọ ni ki a sọ akọmalu na li okuta pa bi o ti wù ki o ṣe, ki a má si ṣe jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn ọrùn oni-akọmalu na yio mọ́. 29 Ṣugbọn bi o ba ṣepe akọmalu na a ti ma fi iwo rẹ̀ kàn nigba atijọ, ti a si ti kìlọ fun oluwa rẹ̀, ti kò si sé e mọ, ṣugbọn ti o pa ọkunrin tabi obinrin, akọmalu na li a o sọ li okuta pa, oluwa rẹ̀ li a o si lù pa pẹlu. 30 Bi o ba si ṣepe a bù iye owo kan fun u, njẹ iyekiye ti a bù fun u ni yio fi ṣe irapada ẹmi rẹ̀. 31 Iba kàn ọmọkunrin, tabi iba kàn ọmọbinrin, gẹgẹ bi irú idajọ yi li a o ṣe si i. 32 Bi akọmalu na ba kan ẹrukunrin tabi ẹrubirin; on o si san ọgbọ̀n ṣekeli fadakà fun oluwa rẹ̀, a o si sọ akọmalu na li okuta pa. 33 Bi ẹnikan ba ṣi ihò silẹ, tabi bi ọkunrin kan ba si wà ihò silẹ, ti kò si bò o, ti akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ba bọ́ sinu rẹ̀; 34 Oni-ihò na yio si san; yio si fi owo fun oluwa wọn; okú ẹran a si jẹ́ tirẹ̀. 35 Bi akọmalu ẹnikan ba si pa akọmalu ẹnikeji lara ti o si kú; ki nwọn ki o tà ãye akọmalu, ki nwọn ki o si pín owo rẹ̀; oku ni ki nwọn ki o si pín pẹlu. 36 Tabi bi a ba si mọ̀ pe akọmalu na a ti ma kàn nigba atijọ ti oluwa rẹ̀ kò sé e mọ́; on o fi akọmalu san akọmalu nitõtọ; okú a si jẹ́ tirẹ̀.

Eksodu 22

1 BI ọkunrin kan ba ji akọmalu, tabi agutan kan, ti o si pa a, tabi ti o tà a; yio san akọmalu marun dipò akọmalu kan, ati agutan mẹrin dipò agutan kan. 2 Bi a ba ri olè ti nrunlẹ wọle, ti a si lù u ti o kú, a ki yio ta ẹ̀jẹ silẹ fun u. 3 Bi õrùn ba là bá a, a o ta ẹ̀jẹ silẹ fun u; sisan li on iba san; bi kò ni nkan, njẹ a o tà a nitori olè rẹ̀. 4 Bi a ba ri ohun ti o ji na li ọwọ́ rẹ̀ nitõtọ li ãye, iba ṣe akọmalu, tabi kẹtẹkẹtẹ, tabi agutan; on o san a pada ni meji. 5 Bi ọkunrin kan ba mu ki a jẹ oko tabi agbalá-àjara kan, ti o si tú ẹran rẹ̀ silẹ, ti o si jẹ li oko ẹlomiran; ninu ãyo oko ti ara rẹ̀, ati ninu ãyo agbalá-àjara tirẹ̀, ni yio fi san ẹsan. 6 Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ. 7 Bi ẹnikan ba fi owo tabi ohunèlo fun ẹnikeji rẹ̀ pamọ́; ti a ji i ni ile ọkunrin na; bi a ba mu olè na, ki o san a ni meji. 8 Bi a kò ba mú olè na, njẹ ki a mú bale na wá siwaju awọn onidajọ, bi on kò ba fọwọkàn ẹrù ẹnikeji rẹ̀. 9 Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀. 10 Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i; 11 Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan. 12 Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀. 13 Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya. 14 Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ. 15 Ṣugbọn bi olohun ba wà nibẹ̀, on ki yio san ẹsan: bi o ba ṣe ohun ti a fi owo gbà lò ni, o dé fun owo igbàlo rẹ̀. 16 Bi ọkunrin kan ba si tàn wundia kan ti a kò ti ifẹ́, ti o si mọ̀ ọ, fifẹ́ ni yio si fẹ́ ẹ li aya rẹ̀. 17 Bi baba rẹ̀ ba kọ̀ jalẹ lati fi i fun u, on o san ojì gẹgẹ bi ifẹ́ wundia. 18 Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ajẹ́ ki o wà lãye. 19 Ẹnikẹni ti o ba bá ẹranko dàpọ pipa li a o pa a. 20 Ẹnikẹni ti o ba rubọ si oriṣakoriṣa, bikoṣe si JEHOFA nikanṣoṣo, a o pa a run tútu. 21 Iwọ kò gbọdọ ṣìka si alejò, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni i lara: nitoripe alejò li ẹnyin ti jẹ́ ni ilẹ Egipti. 22 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ opó ni ìya, tabi ọmọ alainibaba. 23 Bi iwọ ba jẹ wọn ni ìyakiya, ti nwọn si kigbe pè mi, emi o gbọ́ igbe wọn nitõtọ. 24 Ibinu mi yio si gboná, emi o si fi idà pa nyin; awọn aya nyin yio si di opó, awọn ọmọ nyin a si di alainibaba. 25 Bi iwọ ba yá ẹnikẹni ninu awọn enia mi li owo ti o ṣe talaka lọdọ rẹ, iwọ ki yio jẹ́ bi agbẹ̀da fun u; bẹ̃ni iwọ ki yio gbẹ̀da lọwọ rẹ̀. 26 Bi o ba ṣepe iwọ gbà aṣọ ẹnikeji rẹ ṣe ògo, ki iwọ ki o si fi i fun u, ki õrùn to wọ̀: 27 Nitori kìki eyi ni ibora rẹ̀, aṣọ rẹ̀ ti yio fi bora ni: kini on o fi bora sùn? yio si ṣe bi o ba kigbe pè mi, emi o gbọ́; nitori alãnu li emi. 28 Iwọ kò gbọdọ gàn awọn onidajọ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bú ijoye kan ninu awọn enia rẹ. 29 Iwọ kò gbọdọ jafara lati mú irè oko rẹ wá, ati ọti rẹ. Akọ́bi awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni iwọ o fi fun mi. 30 Bẹ̃ gẹgẹ ni ki iwọ ki o fi akọmalu ati agutan rẹ ṣe: ijọ́ meje ni ki o ba iya rẹ̀ gbọ́; ni ijọ́ kẹjọ ni ki iwọ ki o fi i fun mi. 31 Ẹnyin o si jẹ́ enia mimọ́ fun mi; nitorina ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹran ti a ti ọwọ ẹranko igbẹ́ fàya; ajá ni ki ẹnyin ki o wọ́ ọ fun.

Eksodu 23

1 IWỌ kò gbọdọ gbà ìhin eke: máṣe li ọwọ́ si i pẹlu enia buburu lati ṣe ẹlẹri aiṣododo. 2 Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ̀ li ọ̀ran ki o tẹ̀ si ọ̀pọ enia lati yi ẹjọ́ po. 3 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbè talaka li ẹjọ́ rẹ̀. 4 Bi iwọ ba bá akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ọtá rẹ ti o ṣina, ki iwọ ki o mú u pada fun u wá nitõtọ. 5 Bi iwọ ba ri kẹtẹkẹtẹ ẹniti o korira rẹ, ti o dubulẹ labẹ ẹrù rẹ̀, ti iwọ iba yẹra lati bá a tú u, iwọ o bá a tú u nitõtọ. 6 Iwọ kò gbọdọ yi ẹjọ́ talaka rẹ po li ọ̀ran rẹ̀. 7 Takéte li ọ̀ran eke; ati alaiṣẹ ati olododo ni iwọ kò gbọdọ pa: nitoriti emi ki yio dá enia buburu lare. 8 Iwọ kò gbọdọ gbà ọrẹ: nitori ọrẹ ni ifọ́ awọn ti o riran loju, a si yi ọ̀ran awọn olododo po. 9 Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ pọ́n alejò kan loju: ẹnyin sa ti mọ̀ inu alejò, nitoriti ẹnyin ti jẹ́ alejò ni ilẹ Egipti. 10 Ọdún mẹfa ni iwọ o si gbìn ilẹ rẹ, on ni iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ. 11 Ṣugbọn li ọdún keje iwọ o jẹ ki o simi, ki o si gbé jẹ; ki awọn talaka enia rẹ ki o ma jẹ ninu rẹ̀: eyiti nwọn si fisilẹ ni ki ẹran igbẹ ki o ma jẹ. Irú bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe si agbalá-àjara, ati agbalá-olifi rẹ. 12 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣe iṣẹ rẹ, ni ijọ́ keje ki iwọ ki o si simi: ki akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ ki o le simi, ki a le tù ọmọ iranṣẹbinrin rẹ, ati alejò, lara. 13 Ati li ohun gbogbo ti mo wi fun nyin, ẹ ma ṣọra: ki ẹ má si ṣe iranti orukọ oriṣakoriṣa ki a má ṣe gbọ́ ọ li ẹnu nyin. 14 Ni ìgba mẹta ni iwọ o ṣe ajọ fun mi li ọdún. 15 Iwọ o kiyesi ajọ aiwukàra: ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, bi mo ti pa a laṣẹ fun ọ, li akokò oṣù Abibu (nitori ninu rẹ̀ ni iwọ jade kuro ni Egipti); a kò gbọdọ ri ẹnikan niwaju mi li ọwọ́ ofo: 16 Ati ajọ ikore, akọ́so iṣẹ rẹ, ti iwọ gbìn li oko rẹ: ati ajọ ikore oko, li opin ọdún, nigbati iwọ ba ṣe ikore iṣẹ oko rẹ tán. 17 Ni ìgba mẹta li ọdún ni gbogbo awọn ọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa JEHOFA. 18 Iwọ kò gbọdọ ta ọrẹ ẹ̀jẹ ẹbọ mi ti on ti àkara wiwu; bẹ̃li ọrá ẹbọ ajọ mi kò gbọdọ kù titi di ojumọ́. 19 Akọ́ka eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o múwa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀. 20 Kiyesi i, emi rán angeli kan siwaju rẹ lati pa ọ mọ́ li ọ̀na, ati lati mú ọ dé ibi ti mo ti pèse silẹ. 21 Kiyesi ara lọdọ rẹ̀, ki o si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, máṣe bi i ninu; nitoriti ki yio dari irekọja nyin jì nyin, nitoriti orukọ mi mbẹ lara rẹ̀. 22 Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin. 23 Nitoriti angeli mi yio ṣaju rẹ, yio si mú ọ dé ọdọ awọn enia Amori, ati awọn Hitti, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: emi a si ke wọn kuro. 24 Iwọ kò gbọdọ tẹriba fun oriṣa wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn, ki o má si ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: bikoṣepe ki iwọ ki o fọ́ wọn tútu, ki iwọ ki o si wó ere wọn palẹ. 25 Ẹnyin o si ma sìn OLUWA Ọlọrun nyin, on o si busi onjẹ rẹ, ati omi rẹ; emi o si mú àrun kuro lãrin rẹ. 26 Obinrin kan ki yio ṣẹ́nu, bẹ̃ni ki yio yàgan ni ilẹ rẹ: iye ọjọ́ rẹ li emi ó fi kún. 27 Emi o rán ẹ̀ru mi siwaju rẹ, emi o si dà gbogbo awọn enia rú ọdọ ẹniti iwọ o dé, emi o si mu gbogbo awọn ọtá rẹ yi ẹ̀hin wọn dà si ọ. 28 Emi o si rán agbọ́n siwaju rẹ, ti yio lé awọn enia Hifi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn enia Hitti kuro niwaju rẹ. 29 Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju rẹ li ọdún kan; ki ilẹ na ki o má ba di ijù, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba rẹ̀ si ọ. 30 Diẹdiẹ li emi o ma lé wọn jade kuro niwaju rẹ, titi iwọ o fi di pupọ̀, ti iwọ o si tẹ̀ ilẹ na dó. 31 Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ. 32 Iwọ kò gbọdọ bá wọn ṣe adehùn, ati awọn oriṣa wọn pẹlu. 33 Nwọn kò gbọdọ joko ni ilẹ rẹ, ki nwọn ki o má ba mu ọ ṣẹ̀ si mi: nitori bi iwọ ba sìn oriṣa wọn, yio ṣe idẹkùn fun ọ nitõtọ.

Eksodu 24

1 O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére. 2 Mose nikanṣoṣo ni yio si sunmọ OLUWA; ṣugbọn awọn wọnyi kò gbọdọ sunmọ tosi; bẹ̃li awọn enia kò gbọdọ bá a gòke lọ. 3 Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA, ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohùn kan dahùn wipe, Gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA wi li awa o ṣe. 4 Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila. 5 O si rán awọn ọdọmọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si fi akọmalu ru ẹbọ alafia si OLUWA. 6 Mose si mú àbọ ẹ̀jẹ na o si fi i sinu awokòto; ati àbọ ẹ̀jẹ na o fi wọ́n ara pẹpẹ na. 7 O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn. 8 Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi. 9 Nigbana ni Mose, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli gòke lọ: 10 Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀. 11 Kò si nà ọwọ́ rẹ̀ lé awọn ọlọlá ọmọ Israeli: nwọn si ri Ọlọrun, nwọn si jẹ, nwọn si mu. 12 OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn. 13 Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun. 14 O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá. 15 Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ. 16 Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá. 17 Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli. 18 Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.

Eksodu 25

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú ọrẹ fun mi wá: lọwọ olukuluku enia ti o ba fifunni tinutinu ni ki ẹnyin ki o gbà ọrẹ mi. 3 Eyi si li ọrẹ ti ẹnyin o gbà lọwọ wọn; wurà, ati fadakà, ati idẹ; 4 Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ, ati irun ewurẹ; 5 Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu. 6 Oróro fun fitila, olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; 7 Okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. 8 Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn. 9 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e. 10 Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀. 11 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, ninu ati lode ni iwọ o fi bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà sori rẹ̀ yiká. 12 Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi wọn si igun mẹrin rẹ̀; oruka meji yio si wà li apa kini rẹ̀, oruka meji yio si wà li apa keji rẹ̀. 13 Iwọ o si ṣe ọpá ṣittimu, ki iwọ ki o si fi wurà bò wọn. 14 Iwọ o si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, ki a le ma fi wọn gbé apoti na. 15 Ọpá wọnni yio si ma wà ninu oruka apoti na: a ki yio si yọ wọn kuro ninu rẹ̀. 16 Iwọ o si fi ẹrí ti emi o fi fun ọ sinu apoti nì. 17 Iwọ o si fi kìki wurà ṣe itẹ-anu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀. 18 Iwọ o si ṣe kerubu wurà meji; ni iṣẹ lilù ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ni ìku itẹ́-ãnu na mejeji. 19 Si ṣe kerubu kini ni ìku kan, ati kerubu keji ni ìku keji: lati itẹ́-ãnu ni ki ẹnyin ki o ṣe awọn kerubu na ni ìku rẹ̀ mejeji. 20 Awọn kerubu na yio si nà iyẹ́-apa wọn si oke, ki nwọn ki o fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, ki nwọn ki o si kọjusi ara wọn; itẹ́-ãnu na ni ki awọn kerubu na ki o kọjusi. 21 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu na sori apoti na; ati ninu apoti na ni iwọ o fi ẹri ti emi o fi fun ọ si. 22 Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli. 23 Iwọ o si ṣe tabili igi ṣittimu kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀. 24 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 25 Iwọ o si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, iwọ o si ṣe igbáti wurà si eti rẹ̀ yiká. 26 Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà li ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹrin. 27 Li abẹ igbáti na li oruka wọnni yio wà, fun ibi ọpá lati ma fi rù tabili na. 28 Iwọ o si ṣe ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi wurà bò wọn, ki a le ma fi wọn rù tabili na. 29 Iwọ o si ṣe awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, ati awo rẹ̀, lati ma fi dà: kìki wurà ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn. 30 Iwọ o si ma gbé àkara ifihàn kalẹ lori tabili na niwaju mi nigbagbogbo. 31 Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́: 32 Ẹka mẹfa ni yio yọ ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha keji: 33 Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na. 34 Ati ninu ọpá-fitila na li ago mẹrin yio wà ti a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi wọn ati itanna wọn. 35 Irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, gẹgẹ bi ẹka rẹ̀ mẹfẹfa ti o ti ara ọpá-fitila na yọ jade. 36 Irudi wọn ati ẹka wọn ki o ri bakanna: ki gbogbo rẹ̀ ki o jẹ́ lilù kìki wurà kan. 37 Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀. 38 Ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, kìki wurà ni ki o jẹ́. 39 Talenti kan kìki wurà ni ki o fi ṣe e, pẹlu gbogbo ohunèlo wọnyi. 40 Si kiyesi i, ki iwọ ki o ṣe wọn gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, ti a fihàn ọ lori oke.

Eksodu 26

1 IWỌ o fi aṣọ-tita mẹwa ṣe agọ́ na; aṣọ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ti on ti awọn kerubu iṣẹ ọlọnà ni ki iwọ ki o ṣe wọn. 2 Ina aṣọ-tita kan ki o jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ibò aṣọ-tita kan igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na ni ki o jẹ́ ìwọn kanna. 3 Aṣọ-tita marun ni ki a solù mọ́ ara wọn; ati aṣọ-tita marun keji ni ki a solù mọ́ ara wọn. 4 Iwọ o si ṣe ojóbo aṣọ-alaró si eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù, ati bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe li eti ikangun aṣọ-tita keji, ni ibi isolù keji. 5 Ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ-tita kan, ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o si ṣe si eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji; ki ojóbo ki o le kọ́ ara wọn. 6 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, iwọ o si fi ikọ́ na fà awọn aṣọ-tita so: on o si jẹ́ agọ́ kan. 7 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ, lati ṣe ibori sori agọ́ na: aṣọ-tita mọkanla ni iwọ o ṣe e. 8 Ìna aṣọ-tita kan yio jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ati ibò aṣọ-tita kan yio jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla na yio si jẹ́ ìwọn kanna. 9 Iwọ o si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, iwọ o si ṣẹ aṣọ-tita kẹfa po ni meji niwaju agọ́ na. 10 Iwọ o si ṣe ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita na, ti o yọ si ode jù ninu isolù, ati ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù. 11 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ, ki o si fi ikọ́ wọnni sinu ojóbo, ki o si fi so agọ́ na pọ̀, yio si jẹ́ ọkan. 12 Ati iyokù ti o kù ninu aṣọ-tita agọ́ na, àbọ aṣọ-tita ti o kù, yio rọ̀ sori ẹhin agọ na. 13 Ati igbọnwọ kan li apa kan, ati igbọnwọ kan li apa keji, eyiti o kù ni ìna aṣọ-tita agọ́ na, yio si rọ̀ si ìha agọ́ na ni ìha ihin ati ni ìha ọhún, lati bò o. 14 Iwọ o si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori rẹ̀. 15 Iwọ o si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo. 16 Igbọnwọ mẹwa ni gigùn apáko na, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibò apáko kan. 17 Ìtẹbọ meji ni ki o wà li apáko kan, ti o tò li ẹsẹ-ẹsẹ̀ si ara wọn: bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo apáko agọ́ na. 18 Iwọ o si ṣe apáko agọ́ na, ogún apáko ni ìha gusù si ìha gusù. 19 Iwọ o si ṣe ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ meji na, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ meji na; 20 Ati ìha keji agọ́ na ni ìha ariwa, ogún apáko ni yio wà nibẹ̀: 21 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà wọn; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko na kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji. 22 Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn apáko mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe. 23 Ati apáko meji ni iwọ o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha ẹhin rẹ̀. 24 A o si so wọn pọ̀ nisalẹ, a o si so wọn pọ̀ li oke ori rẹ̀ si oruka kan: bẹ̃ni yio si ṣe ti awọn mejeji; nwọn o si ṣe ti igun mejeji. 25 Nwọn o si jẹ́ apáko mẹjọ, ati ihò-ìtẹbọ fadakà wọn, ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji. 26 Iwọ o si ṣe ọpá idabu igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na, 27 Ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha keji agọ́ na, ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha agọ́ na, fun ìha mejeji ni ìha ìwọ-õrùn. 28 Ati ọpá ãrin li agbedemeji apáko wọnni yio ti ìku dé ìku. 29 Iwọ o si fi wurà bò apáko wọnni, iwọ o si fi wurà ṣe oruka wọn li àye fun ọpá idabu wọnni: iwọ o si fi wurà bò ọpá idabu wọnni. 30 Iwọ o si gbé agọ́ na ró, gẹgẹ bi apẹrẹ rẹ̀, ti a fihàn ọ lori oke. 31 Iwọ o si ṣe aṣọ-ikele alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti iṣẹ ọlọnà: ti on ti awọn kerubu nì ki a ṣe e: 32 Iwọ o si fi rọ̀ sara opó igi ṣittimu mẹrin, ti a fi wurà bò, wurà ni ikọ́ wọn lori ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrẹrin na. 33 Iwọ o si ta aṣọ-ikele na si abẹ ikọ́ wọnni, ki iwọ ki o le mú apoti ẹrí nì wá si inu aṣọ-ikele nì: aṣọ-ikele nì ni yio si pinya lãrin ibi mimọ́ ati ibi mimọ́ julọ fun nyin. 34 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu sori apoti ẹrí nì, ni ibi mimọ́ julọ. 35 Iwọ o si gbé tabili na kà ẹhin ode aṣọ-ikele nì, ati ọpá-fitila nì kọjusi tabili na ni ìha agọ́ na ni ìha gusù: iwọ o si gbé tabili na kà ìha ariwa. 36 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita kan fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na, ti aṣọ-alaró, ti elesè-aluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe. 37 Iwọ o si ṣe opó igi ṣittimu marun fun aṣọ-tita na, ki o si fi wurà bò wọn; ati ikọ́ wọn wurà: iwọ o si dà ihò-ìtẹbọ idẹ marun fun wọn.

Eksodu 27

1 IWỌ o si tẹ́ pẹpẹ igi ṣittimu kan, ìna rẹ̀ igbọnwọ marun, ati ìbú rẹ̀ igbọnwọ marun; ìwọn kan ni ìha mẹrẹrin: igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀. 2 Iwọ o si ṣe iwo rẹ̀ si ori igun mẹrẹrin rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀: iwọ o si fi idẹ bò o. 3 Iwọ o si ṣe tasà rẹ̀ lati ma gbà ẽru rẹ̀, ati ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀ ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo-iná rẹ̀ wọnni: gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ni iwọ o fi idẹ ṣe. 4 Iwọ o si ṣe oju-àro idẹ fun u ni iṣẹ-àwọn; lara àwọn na ni ki iwọ ki o ṣe oruka mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀. 5 Iwọ o si fi si abẹ ayiká pẹpẹ na nisalẹ, ki àwọn na ki o le dé idaji pẹpẹ na. 6 Iwọ o si ṣe ọpá fun pẹpẹ na, ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi idẹ bò wọn. 7 A o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ oruka wọnni, ọpá wọnni yio si wà ni ìha mejeji pẹpẹ na, lati ma fi rù u. 8 Onihò ninu ni iwọ o fi apáko ṣe e: bi a ti fihàn ọ lori oke, bẹ̃ni ki nwọn ki o ṣe e. 9 Iwọ o si ṣe agbalá agọ́ na: ni ìha gusù lọwọ ọtún li aṣọ-tita agbalá ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti ọgọrun igbọnwọ ìna, yio wà ni ìha kan: 10 Ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ wọn, ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà. 11 Ati bẹ̃ gẹgẹ niti ìha ariwa ni gigùn aṣọ-tita wọnni yio jẹ́ ọgọrun igbọnwọ ni ìna wọn, ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ rẹ̀ ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà. 12 Ati niti ibú agbalá na, ni ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ yio wà: opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa. 13 Ati ibú agbalá na ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn yio jẹ́ ãdọta igbọnwọ. 14 Aṣọ-tita apakan ẹnu-ọ̀na na yio jẹ́ igbọnwọ mẹdogun: opó wọn mẹta, ihò-ìtẹbọ wọn mẹta. 15 Ati ni ìha keji ni aṣọ-tita igbọnwọ mẹdogun yio wà: opó wọn mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹta. 16 Ati fun ẹnu-ọ̀na agbalá na aṣọ-tita ogún igbọnwọ yio wà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe: opó wọn mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹrin. 17 Gbogbo opó ti o yi sarè na ká li a o si fi ọpá fadakà sopọ̀; ikọ́ wọn yio jẹ́ fadakà, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ. 18 Ìna agbalá na ki o jẹ́ ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ arãdọtọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ igbọnwọ marun, ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ. 19 Gbogbo ohun-èlo agọ́ na, ni gbogbo ìsin rẹ̀, ati gbogbo ekàn rẹ̀, ati gbogbo ekàn agbalá na ki o jẹ́ idẹ. 20 Iwọ o si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú oróro olifi daradara ti a gún fun ọ wá, fun imọlẹ, lati mu ki fitila ki o ma tàn nigbagbogbo. 21 Li agọ́ ajọ lẹhin ode aṣọ-ikele ti o wà niwaju ẹ̀rí na, Aaroni ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ ni yio tọju rẹ̀ lati alẹ titi di owurọ̀ niwaju OLUWA: yio si di ìlana lailai ni irandiran wọn lọdọ awọn ọmọ Israeli.

Eksodu 28

1 IWỌ si mú Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀ si ọdọ rẹ, kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi, ani Aaroni, Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni. 2 Iwọ o si dá aṣọ mimọ́ fun Aaroni arakunrin rẹ fun ogo ati fun ọṣọ́. 3 Iwọ o si sọ fun gbogbo awọn ti o ṣe amoye, awọn ẹniti mo fi ẹmi ọgbọ́n kún, ki nwọn ki o le dá aṣọ Aaroni lati yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 4 Wọnyi si li aṣọ ti nwọn o dá; igbàiya kan, ati ẹ̀wu-efodi, ati aṣọ igunwà, ati ẹ̀wu-awọtẹlẹ ọlọnà, fila, ati ọjá-amure: nwọn o si dá aṣọ mimọ́ wọnyi fun Aaroni arakunrin rẹ, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 5 Nwọn o si mú wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ. 6 Nwọn o si ṣe ẹ̀wu-efodi ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ti ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ iṣẹ ọlọnà, 7 Yio ní aṣọ ejika meji ti o solù li eti rẹ̀ mejeji; bẹ̃ni ki a so o pọ̀. 8 Ati onirũru-ọnà ọjá rẹ̀, ti o wà lori rẹ̀ yio ri bakanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 9 Iwọ o si mú okuta oniki meji, iwọ o si fin orukọ awọn ọmọ Israeli sara wọn: 10 Orukọ awọn mẹfa sara okuta kan, ati orukọ mẹfa iyokù sara okuta keji, gẹgẹ bi ìbí wọn. 11 Iṣẹ-ọnà afin-okuta, bi ifin èdidi-àmi, ni iwọ o fin okuta mejeji gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli: iwọ o si dè wọn si oju-ìde wurà. 12 Iwọ o si fi okuta mejeji si ejika ẹ̀wu-efodu na, li okuta iranti fun awọn ọmọ Israeli; Aaroni yio si ma rù orukọ wọn niwaju OLUWA li ejika rẹ̀ mejeji fun iranti. 13 Iwọ o si ṣe oju-ìde wurà: 14 Ati okùn ẹ̀wọn meji ti kìki wurà; iṣẹ ọnà-lilọ ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ki iwọ ki o si so okùn ẹ̀wọn iṣẹ ọnà-lilọ ni si oju-ìde na. 15 Iwọ o si fi iṣẹ ọgbọ́n na ṣe igbàiya idajọ na; nipa iṣẹ-ọnà ẹ̀wu-efodi ni iwọ o ṣe e; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododò, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ni iwọ o fi ṣe e. 16 Iha mẹrin ọgbọgba ni ki iwọ ki o ṣe e ni iṣẹpo meji; ika kan ni ìna rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀. 17 Iwọ o si tò ìto okuta sinu rẹ̀, ẹsẹ̀ okuta mẹrin: ẹsẹ̀ kini, sardiu, topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini: 18 Ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi; 19 Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu; 20 Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, ati oniki, ati jasperi: a o si tò wọn si oju wurà ni didè wọn. 21 Okuta wọnni yio si wà gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn; bi ifin edidi-àmi; olukuluku gẹgẹ bi orukọ rẹ̀ ni nwọn o wà fun ẹ̀ya Israeli mejejila. 22 Iwọ o si ṣe okùn ẹ̀wọn kìka wurà iṣẹ ọnà-lilọ si igbàiya na. 23 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji sara igbàiya na, iwọ o si fi oruka meji na si eti mejeji igbàiya na. 24 Iwọ o si fi okùn ẹ̀wọn wurà mejeji sinu oruka meji wọnni li eti igbàiya na. 25 Ati eti ẹ̀wọn meji ni ki iwọ ki o so mọ́ oju-ìde mejeji, ki o si fi si ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀. 26 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si eti mejeji igbàiya na li eti rẹ̀, ti o wà ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inú. 27 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi mejeji nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ti o kọjusi isolù rẹ̀, loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na. 28 Nwọn o si fi oruka rẹ̀ so igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi na ti on ti ọjá àwọn alaró, ki o le wà loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ki a má si ṣe tú igbàiya na kuro lara ẹ̀wu-efodi na. 29 Aaroni yio si ma rù orukọ awọn ọmọ Israeli ninu igbàiya idajọ li àiya rẹ̀, nigbati o ba nwọ̀ ibi mimọ́ nì lọ, fun iranti nigbagbogbo niwaju OLUWA. 30 Iwọ o si fi Urimu on Tummimu sinu igbàiya idajọ; nwọn o si wà li àiya Aaroni, nigbati o ba nwọle lọ niwaju OLUWA; Aaroni yio si ma rù idajọ awọn ọmọ Israeli li àiya rẹ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA. 31 Iwọ o si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni kìki aṣọ-alaró. 32 Oju ọrùn yio si wà lãrin rẹ̀ fun ori; ọjá iṣẹti yio si wà yi oju rẹ̀ ká, iṣẹ-oniṣọnà gẹgẹ bi ẹ̀wu ogun, ki o má ba fàya. 33 Ati ni iṣẹti rẹ̀ nisalẹ ni iwọ o ṣe pomegranate aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, yi iṣẹti rẹ̀ ká; ati ṣaworo wurà lãrin wọn yiká; 34 Ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, li eti iṣẹti aṣọ igunwa na yiká. 35 On o si wà lara Aaroni lati ma fi ṣiṣẹ: a o si ma gbọ́ iró rẹ̀ nigbati o ba wọ̀ ibi mimọ́ lọ niwaju OLUWA, ati nigbati o ba si njade bọ̀, ki o má ba kú. 36 Iwọ o si ṣe awo ni kìki wurà, iwọ o si fin sara rẹ̀, gẹgẹ bi fifin èdidi-àmi pe, MIMỌ́ SI OLUWA. 37 Iwọ o si fi i sara ọjá-àwọn alaró, ki o le ma wà lara fila nì, niwaju fila na ni ki o wà. 38 On o si ma wà niwaju ori Aaroni, ki Aaroni le ma rù ẹ̀ṣẹ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yio si yàsimimọ́, ninu gbogbo ẹ̀bun mimọ́ wọn: on o si ma wà niwaju ori rẹ̀ nigbagbogbo, ki OLUWA ki o le ni inudidùn si wọn. 39 Iwọ o si fi ọ̀gbọ didara wun ẹ̀wu-awọtẹlẹ, iwọ o si fi ọ̀gbọ didara ṣe fila, iwọ o si fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe ọjá-amure. 40 Iwọ o si dá ẹ̀wu-awọtẹlẹ fun awọn ọmọ Aaroni, iwọ o si dá ọjá-amure fun wọn, iwọ o si dá fila fun wọn, fun ogo ati fun ọṣọ́. 41 Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 42 Iwọ o si dá ṣòkoto ọ̀gbọ fun wọn lati ma fi bò ìhoho wọn, ki o ti ibadi dé itan: 43 Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.

Eksodu 29

1 EYI si li ohun ti iwọ o ṣe si wọn lati yà wọn simimọ́, lati ma ṣe alufa fun mi: mú ẹgbọ̀rọ akọmalu kan, ati àgbo meji ti kò li abùku. 2 Ati àkara alaiwu, ati adidùn àkara alaiwu ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si lori; iyẹfun alikama ni ki o fi ṣe wọn. 3 Iwọ o si fi wọn sinu agbọ̀n kan, iwọ o si mú wọn wá ninu agbọ̀n na, pẹlu akọmalu na ati àgbo mejeji. 4 Iwọ o si mú Aaroni pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn. 5 Iwọ o si mú aṣọ wọnni, iwọ o si fi ẹ̀wu-awọtẹlẹ nì wọ̀ Aaroni, ati aṣọ igunwa efodi, ati efodi, ati igbàiya, ki o si fi onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi dì i. 6 Iwọ o si fi fila nì dé e li ori, iwọ o si fi adé mimọ́ nì sara fila na. 7 Nigbana ni iwọ o si mú oróro itasori, iwọ o si dà a si i li ori, iwọ o si fi oróro yà a simimọ́. 8 Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá tosi, iwọ o si wọ̀ wọn li ẹ̀wu. 9 Iwọ o si dì wọn li ọjá-amure, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si fi fila dé wọn: iṣẹ-alufa yio si ma jẹ́ ti wọn ni ìlana titi aiye: iwọ o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́. 10 Iwọ o si mú akọmalu na wá siwaju agọ́ ajọ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé akọmalu na li ori. 11 Iwọ o si pa akọmalu na niwaju OLUWA, loju ọ̀na agọ́ ajọ. 12 Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, iwọ o si fi ika rẹ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na; iwọ o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si ìha isalẹ pẹpẹ na. 13 Iwọ o si mú gbogbo ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bori ẹ̀dọ, ati ti iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, iwọ o si sun u lori pẹpẹ na. 14 Ṣugbọn ẹran akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati igbẹ rẹ̀, on ni ki iwọ ki o fi iná sun lẹhin ode ibudó: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 15 Iwọ o si mú àgbo kan; ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori. 16 Iwọ o si pa àgbo na, iwọ o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀, iwọ o si fi i wọ́n pẹpẹ na yiká. 17 Iwọ o si kun àgbo na, iwọ o si fọ̀ ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀, iwọ o si fi wọn lé ara wọn, ati lé ori rẹ̀. 18 Iwọ o si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ na: ẹbọ sisun ni si OLUWA: õrùn didùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 19 Iwọ o si mú àgbo keji; Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori. 20 Nigbana ni ki iwọ ki o pa àgbo na, ki o si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si eti ọtún awọn ọmọ rẹ̀, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn, ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n pẹpẹ na yiká. 21 Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 22 Iwọ o si mú ọrá, ati ìru ti o lọrá ti àgbo na, ati ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ̀, ati iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, ati itan ọtún; nitori àgbo ìyasimimọ́ ni: 23 Ati ìṣu àkara kan, ati àkara kan ti a fi oróro din, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan kuro ninu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA: 24 Iwọ o si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni lọwọ, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀; iwọ o si ma fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 25 Iwọ o si gbà wọn li ọwọ́ wọn, iwọ o si sun wọn lori pẹpẹ na li ẹbọ sisun, fun õrùn didùn niwaju OLUWA: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 26 Iwọ o si mú igẹ̀ àgbo ìyasimimọ́ Aaroni, iwọ o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; ìpín tirẹ li eyinì. 27 Iwọ o si yà igẹ̀ ẹbọ fifì na simimọ́, ati itan ẹbọ agbesọsoke, ti a fì, ti a si gbesọsoke ninu àgbo ìyasimimọ́ na, ani ninu eyiti iṣe ti Aaroni, ati ninu eyiti iṣe ti awọn ọmọ rẹ̀: 28 Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA. 29 Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn. 30 Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì. 31 Iwọ o si mú àgbo ìyasimimọ́ nì, iwọ o si bọ̀ ẹran rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan. 32 Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si jẹ ẹran àgbo na, ati àkara na ti o wà ninu agbọ̀n nì, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 33 Nwọn o si jẹ nkan wọnni ti a fi ṣètutu na, lati yà wọn simimọ́, ati lati sọ wọn di mimọ́: ṣugbọn alejò ni kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, nitoripe mimọ́ ni. 34 Bi ohun kan ninu ẹran ìyasimimọ́ na, tabi ninu àkara na, ba kú titi di ojumọ́, nigbana ni ki iwọ ki o fi iná sun iyokù: a ki yio jẹ ẹ, nitoripe mimọ́ ni. 35 Bayi ni iwọ o si ṣe fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti mo paṣẹ fun ọ: ijọ́ meje ni iwọ o fi yà wọn simimọ́. 36 Iwọ o si ma pa akọmalu kọkan li ojojumọ́ ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu: iwọ o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, nigbati iwọ ba ṣètutu si i tán, iwọ o si ta oróro si i lati yà a simimọ́. 37 Ni ijọ́ meje ni iwọ o fi ṣètutu si pẹpẹ na, iwọ o si yà a simimọ́: on o si ṣe pẹpẹ mimọ́ julọ; ohunkohun ti o ba fọwọkàn pẹpẹ na, mimọ́ ni yio jẹ́. 38 Njẹ eyi ni iwọ o ma fi rubọ lori pẹpẹ na; ọdọ-agutan meji ọlọdún kan li ojojumọ́ lailai. 39 Ọdọ-agutan kan ni iwọ o fi rubọ li owurọ̀; ati ọdọ-agutan keji ni iwọ o fi rubọ li aṣalẹ: 40 Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin hini oróro ti a gún pòlu; ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ mimu, fun ọdọ-agutan ekini. 41 Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o pa rubọ li aṣalẹ, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi ẹbọ jijẹ owurọ̀, ati gẹgẹ bi ẹbọ mimu rẹ̀, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 42 Ẹbọ sisun titilai ni yio ṣe lati irandiran nyin li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA: nibiti emi o ma bá nyin pade lati ma bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀. 43 Nibẹ̀ li emi o ma pade awọn ọmọ Israeli; a o si fi ogo mi yà agọ́ na simimọ́. 44 Emi o si yà agọ́ ajọ na simimọ́, ati pẹpẹ nì: emi o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́, lati ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 45 Emi o si ma gbé ãrin awọn ọmọ Israeli, emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn. 46 Nwọn o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun wọn, ti o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá, ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn: emi li OLUWA Ọlọrun wọn.

Eksodu 30

1 IWỌ o si ṣe pẹpẹ kan lati ma jó turari lori rẹ̀: igi ṣittimu ni ki iwọ ki o fi ṣe e. 2 Igbọnwọ kan ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀; ìha mẹrin ọgbọgba ni ki o jẹ́: igbọnwọ meji si ni giga rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀. 3 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, oke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀; iwọ o si ṣe igbáti wurà yi i ká. 4 Ati oruka wurà meji ni ki iwọ ki o ṣe nisalẹ igbáti rẹ̀, ni ìha igun rẹ̀ meji, li ẹgbẹ rẹ̀ mejeji ni ki iwọ ki o ṣe e si; nwọn o si jasi ipò fun ọpá wọnni, lati ma fi gbé e. 5 Iwọ o si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, iwọ o si fi wurà bò wọn. 6 Iwọ o si gbé e kà iwaju aṣọ-ikele nì ti o wà lẹba apoti ẹrí, niwaju itẹ́-ãnu ti o wà lori apoti ẹrí nì, nibiti emi o ma bá ọ pade. 7 Aaroni yio si ma jó turari didùn lori rẹ̀; li orowurọ̀, nigbati o ba tun fitila wọnni ṣe, on o si ma jó o lori rẹ̀. 8 Nigbati Aaroni ba si tàn fitila wọnni li aṣalẹ, yio si ma jó turari lori rẹ̀, turari titilai niwaju OLUWA lati irandiran nyin. 9 Ẹnyin kò gbọdọ mú ajeji turari wá sori rẹ̀, tabi ẹbọ sisun, tabi ẹbọ onjẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ dà ẹbọ ohun mimu sori rẹ̀. 10 Aaroni yio si ma fi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ ètutu ṣètutu lori iwo rẹ̀ lẹ̃kan li ọdún: yio ṣètutu lori rẹ̀ lẹ̃kan li ọdun lati irandiran nyin: mimọ́ julọ ni si OLUWA. 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn. 13 Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA. 14 Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA. 15 Olowo ki o san jù bẹ̃ lọ, bẹ̃li awọn talaka kò si gbọdọ di li àbọ ṣekeli, nigbati nwọn ba mú ọrẹ wá fun OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin. 16 Iwọ o si gbà owo ètutu na lọwọ awọn ọmọ Israeli, iwọ o si fi i lelẹ fun ìsin agọ́ ajọ; ki o le ma ṣe iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin. 17 OLUWA si sọ fun Mose pe, 18 Iwọ o si ṣe agbada idẹ kan, ati ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fun wiwẹ̀: iwọ o si gbẹ́ e kà agbedemeji agọ́ ajọ, ati pẹpẹ nì, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀. 19 Nitori Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn nibẹ̀: 20 Nigbati nwọn ba nwọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nwọn o fi omi wẹ̀ ki nwọn ki o má ba kú: tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ nì lati ṣe ìsin, lati ru ẹbọ sisun ti a fi iná ṣe si OLUWA: 21 Nwọn o si wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn, ki nwọn ki o má ba kú: yio si di ìlana fun wọn lailai, fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lati irandiran wọn. 22 OLUWA si sọ fun Mose pe, 23 Iwọ mú ãyo olõrùn si ọdọ rẹ, pẹlu ojia sísan ẹdẹgbẹta ṣekeli, ati kinnamoni didùn idameji bẹ̃, ani ãdọtalerugba ṣekeli, ati kalamu didùn ãdọtalerugba ṣekeli, 24 Ati kassia ẹdẹgbẹta ṣekeli, ṣekeli ibi mimọ́, ati hini oróro olifi kan: 25 Iwọ o si ṣe e li oróro mimọ́ ikunra, ti a fi ọgbọ́n alapòlu pò: yio si jẹ́ oróro mimọ́ itasori. 26 Iwọ o si ta ninu rẹ̀ sara agọ́ ajọ, ati apoti ẹrí nì, 27 Ati tabili ati ohunèlo rẹ̀ gbogbo, ati ọpáfitila ati ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari, 28 Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀. 29 Iwọ o si yà wọn simimọ́, ki nwọn ki o le ṣe mimọ́ julọ: ohunkohun ti o ba fọwọkàn wọn yio di mimọ́. 30 Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi. 31 Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin. 32 A ko gbọdọ dà a si ara enia, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rẹ̀, ni ìwọn pipò rẹ̀: mimọ́ ni, yio si ma ṣe mimọ́ fun nyin. 33 Ẹnikẹni ti o ba pò bi irú rẹ̀, tabi ẹnikẹni ti o ba fi sara alejò ninu rẹ̀, on li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 34 OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku; 35 Iwọ o si ṣe e ni turari, apòlu nipa ọgbọ́n-ọnà alapòlu, ti a fi iyọ̀ si, ti o dara ti o si mọ́. 36 Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin. 37 Ati ti turari ti iwọ o ṣe, ẹnyin kò gbọdọ ṣe e fun ara nyin ni ìwọn pipò rẹ̀: yio si ṣe mimọ́ fun ọ si OLUWA. 38 Ẹnikẹni ti o ba ṣe irú rẹ̀, lati ma gbõrùn rẹ̀, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

Eksodu 31

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah: 3 Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà. 4 Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, 5 Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. 6 Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ: 7 Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na. 8 Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari; 9 Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀; 10 Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa; 11 Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe. 12 OLUWA si sọ fun Mose pe, 13 Ki iwọ ki o sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ isimi mi li ẹnyin o pamọ́ nitõtọ: nitori àmi ni lãrin emi ati lãrin nyin lati irandiran nyin; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA ti o yà nyin simimọ́. 14 Nitorina ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́ isimi mọ́; nitoripe mimọ́ ni fun nyin: ẹniti o ba bà a jẹ́ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 15 Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ́ keje ni ọjọ́ isimi, mimọ́ ni si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ li ọjọ́ isimi, on li a o si pa nitõtọ. 16 Nitorina li awọn ọmọ Israeli yio ṣe ma pa ọjọ́ isimi mọ́, lati ma kiyesi ọjọ́ isimi lati irandiran wọn, fun majẹmu titilai. 17 Àmi ni iṣe lãrin emi ati lãrin awọn ọmọ Israeli titilai: nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, ni ijọ́ keje o si simi, o si ṣe ìtura. 18 O si fi walã ẹrí meji, walã okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigbati o pari ọ̀rọ bibá a sọ tán lori oke Sinai.

Eksodu 32

1 NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. 2 Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá. 3 Gbogbo awọn enia si kán oruka wurà ti o wà li eti wọn, nwọn si mú wọn tọ̀ Aaroni wá. 4 O si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si fi ohun-ọnà fifin ṣe e, nigbati o si dà a li aworan ẹgbọrọmalu tán: nwọn si wipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ Egipti wá. 5 Nigbati Aaroni si ri i, o tẹ́ pẹpẹ kan niwaju rẹ̀; Aaroni si kede, o si wipe, Ọla li ajọ fun OLUWA. 6 Nwọn si dide ni kùtukutu ijọ́ keji nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si mú ẹbọ alafia wá; awọn enia si joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. 7 OLUWA si sọ fun Mose pe, Lọ, sọkalẹ lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, nwọn ti ṣẹ̀. 8 Nwọn ti yipada kánkan kuro ni ipa-ọ̀na ti mo làsilẹ fun wọn: nwọn ti dá ere ẹgbọrọmalu fun ara wọn, nwọn si ti mbọ ọ, nwọn si ti rubọ si i, nwọn nwipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ̀ Egipti wá. 9 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi ti ri awọn enia yi, si kiyesi i, ọlọrùn lile enia ni: 10 Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla. 11 Mose si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, OLUWA, ẽtiṣe ti ibinu rẹ fi gbona si awọn enia rẹ, ti iwọ fi ipá nla ati ọwọ́ agbara rẹ mú lati ilẹ Egipti jade wá? 12 Nitori kini awọn ara Egipti yio ṣe sọ wipe, Nitori ibi li o ṣe mú wọn jade, lati pa wọn lori oke, ati lati run wọn kuro lori ilẹ? Yipada kuro ninu ibinu rẹ ti o muna, ki o si yi ọkàn pada niti ibi yi si awọn enia rẹ. 13 Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Israeli awọn iranṣẹ rẹ, ẹniti iwọ fi ara rẹ bura fun, ti iwọ si wi fun wọn pe, Emi o mu irú-ọmọ nyin bisi i bi irawọ ọrun, ati gbogbo ilẹ na ti mo ti sọ nì, irú-ọmọ nyin li emi o fi fun, nwọn o si jogún rẹ̀ lailai. 14 OLUWA si yi ọkàn pada niti ibi na ti o ti sọ pe on o ṣe si awọn enia rẹ̀. 15 Mose si yipada, o si sọkalẹ lati ori òke na wá, walã ẹrí meji nì si wà li ọwọ́ rẹ̀; walã ti a kọwe si ni ìha mejeji; lara ekini ati ekeji li a kọwe si. 16 Iṣẹ́ Ọlọrun si ni walã wọnni, ikọwe na ni ikọwe Ọlọrun, a fin i sara walã na. 17 Nigbati Joṣua si gbọ́ ariwo awọn enia na, bi nwọn ti nhó, o wi fun Mose pe, Ariwo ogun mbẹ ni ibudó. 18 Mose si wi pe, Ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nhó nitori iṣẹgun, bẹ̃ni ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nkigbe pe a ṣẹgun wọn: ohùn awọn ti nkọrin ni mo gbọ́ yi. 19 O si ṣe, bi o ti sunmọ ibudó, o si ri ẹgbọrọmalu na, ati agbo ijó: ibinu Mose si ru gidigidi, o si sọ walã wọnni silẹ kuro li ọwọ́ rẹ̀, o si fọ́ wọn nisalẹ òke na. 20 O si mú ẹgbọrọ-malu na ti nwọn ṣe, o si sun u ni iná, o si lọ̀ ọ di ẹ̀tu, o si kù u soju omi, o si mu awọn ọmọ Israeli mu u. 21 Mose si wi fun Aaroni pe, Kili awọn enia wọnyi fi ṣe ọ, ti iwọ fi mú ẹ̀ṣẹ̀ nla wá sori wọn? 22 Aaroni si wipe, Máṣe jẹ ki ibinu oluwa mi ki o gbona: iwọ mọ̀ awọn enia yi pe, nwọn buru. 23 Awọn li o sa wi fun mi pe, Ṣe oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa: bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. 24 Emi si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba ni wurà, ki nwọn ki o kán a kuro; bẹ̃ni nwọn fi fun mi: nigbana li emi fi i sinu iná, ẹgbọrọmalu yi si ti jade wá. 25 Nigbati Mose ri i pe awọn enia na kò ṣe ikoso; nitoriti Aaroni sọ wọn di alailakoso lãrin awọn ti o dide si wọn. 26 Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀. 27 O si wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli, wipe, Ki olukuluku ọkunrin ki o kọ idà rẹ̀ si ẹgbẹ́ rẹ̀, ki ẹ si ma wọle, ki ẹ si ma jade lati ẹnubode dé ẹnubode já gbogbo ibudó, olukuluku ki o si pa arakunrin rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa ẹgbẹ rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa aladugbo rẹ̀. 28 Awọn ọmọ Lefi si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose: awọn ti o ṣubu ninu awọn enia li ọjọ́ na to ìwọn ẹgbẹdogun enia. 29 Mose sa ti wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ li oni fun OLUWA, ani olukuluku ọkunrin lara ọmọ rẹ̀, ati lara arakunrin rẹ̀; ki o le fi ibukún si nyin lori li oni. 30 O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Mose wi fun awọn enia pe, Ẹnyin dá ẹ̀ṣẹ nla: njẹ nisisiyi, emi o gòke tọ̀ OLUWA, bọya emi o ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ nyin. 31 Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wipe, Yẽ, awọn enia wọnyi ti dá ẹ̀ṣẹ nla, nwọn si dá oriṣa wurà fun ara wọn. 32 Nisisiyi, bi iwọ o ba dari ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn; bi bẹ̃ si kọ, emi bẹ̀ ọ, pa mi rẹ́ kuro ninu iwé rẹ ti iwọ ti kọ. 33 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹnikẹni ti o ṣẹ̀ mi, on li emi o parẹ́ kuro ninu iwé mi. 34 Njẹ nisisiyi lọ, ma mú awọn enia na lọ si ibiti mo ti sọ fun ọ: kiyesi i, angeli mi yio ṣaju rẹ: ṣugbọn li ọjọ́ ti emi o ṣe ìbẹwo, emi o bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò lara wọn. 35 OLUWA si yọ awọn enia na lẹnu, nitoriti nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu, ti Aaroni ṣe.

Eksodu 33

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide, gòke lati ihin lọ, iwọ ati awọn enia na ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, si ilẹ ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi i fun: 2 Emi o si rán angeli kan si iwaju rẹ; emi o si lé awọn ara Kenaani, awọn ara Amori, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi jade: 3 Si ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; emi ki yio sa gòke lọ lãrin rẹ; nitori ọlọrùn lile ni iwọ: ki emi ki o má ba run ọ li ọ̀na. 4 Nigbati awọn enia na si gbọ́ ihin buburu yi, nwọn kãnu: enia kan kò si wọ̀ ohun ọṣọ́ rẹ̀. 5 OLUWA si ti wi fun Mose pe, Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, ọlọ́rùn lile ni nyin: bi emi ba gòke wá sãrin rẹ ni iṣẹju kan, emi o si run ọ: njẹ nisisiyi bọ́ ohun ọṣọ́ rẹ kuro lara rẹ, ki emi ki o le mọ̀ ohun ti emi o fi ọ ṣe. 6 Awọn ọmọ Israeli si bọ́ ohun ọṣọ́ wọn kuro lara wọn leti oke Horebu. 7 Mose si mú agọ́ na, o si pa a lẹhin ibudó, li òkere rére si ibudó; o pè e ni Agọ́ ajọ. O si ṣe, olukuluku ẹniti mbère OLUWA o jade lọ si agọ́ ajọ, ti o wà lẹhin ibudó. 8 O si ṣe, nigbati Mose jade lọ si ibi agọ́ na, gbogbo awọn enia a si dide duro, olukuluku a si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀, a ma wò ẹhin Mose, titi yio fi dé ibi agọ́ na. 9 O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ. 10 Gbogbo enia si ri ọwọ̀n awọsanma na o duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: gbogbo enia si dide duro, nwọn si wolẹ sìn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀. 11 OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na. 12 Mose si wi fun OLUWA pe, Wò o, iwọ wi fun mi pe, Mú awọn enia wọnyi gòke lọ: sibẹ̀ iwọ kò jẹ ki emi ki o mọ̀ ẹniti iwọ o rán pẹlu mi. Ṣugbọn iwọ wipe, Emi mọ̀ ọ li orukọ, iwọ si ri ore-ọfẹ li oju mi pẹlu. 13 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni. 14 On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi. 15 On si wi fun u pe, Bi oju rẹ kò ba bá wa lọ, máṣe mú wa gòke lati ihin lọ. 16 Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ? 17 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ. 18 O si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ogo rẹ̀ hàn mi. 19 On si wi fun u pe, Emi o mu gbogbo ore mi kọja niwaju rẹ, emi o si pè orukọ OLUWA niwaju rẹ; emi o si ṣe ore-ọfẹ fun ẹniti emi nfẹ ṣe ore-ọfẹ fun, emi o si ṣe ãnu fun ẹniti emi o ṣe ãnu fun. 20 On si wipe, Iwọ kò le ri oju mi: nitoriti kò sí enia kan ti iri mi, ti si yè. 21 OLUWA si wipe, Wò, ibi kan wà lẹba ọdọ mi, iwọ o si duro lori apata: 22 Yio si ṣe, nigbati ogo mi ba nrekọja, emi o fi ọ sinu palapala apata, emi o si fi ọwọ́ mi bò ọ titi emi o fi rekọja: 23 Nigbati emi o mú ọwọ́ mi kuro, iwọ o si ri akẹhinsi mi: ṣugbọn oju mi li a ki iri.

Eksodu 34

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju: emi o si kọ ọ̀rọ walã ti iṣaju, ti iwọ ti fọ́, sara walã wọnyi. 2 Si mura li owurọ̀, ki iwọ ki o si gún òke Sinai wá li owurọ̀, ki o si wá duro niwaju mi nibẹ̀ lori òke na. 3 Ẹnikẹni ki yio si bá ọ gòke wá, ki a má si ṣe ri ẹnikẹni pẹlu li òke na gbogbo; bẹ̃ni ki a máṣe jẹ ki agbo-agutan tabi ọwọ́-ẹran ki o jẹ niwaju òke na. 4 On si gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju; Mose si dide ni kutukutu owurọ̀, o si gún òke Sinai, bi OLUWA ti paṣẹ fun u, o si mú walã okuta mejeji li ọwọ́ rẹ̀. 5 OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA. 6 OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ; 7 Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin. 8 Mose si yara, o si foribalẹ, o si sìn. 9 On si wipe, Njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi Oluwa, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Oluwa ki o ma bá wa lọ; nitori enia ọlọrùn lile ni; ki o si dari aiṣẹdede wa ati ẹ̀ṣẹ wa jì, ki o si fi wa ṣe iní rẹ. 10 On si wipe, Kiyesi i, emi dá majẹmu kan: emi o ṣe ohun iyanu, niwaju gbogbo awọn enia rẹ irú eyiti a kò ti iṣe lori ilẹ gbogbo rí, ati ninu gbogbo orilẹ-ède: ati gbogbo enia ninu awọn ti iwọ wà, nwọn o ri iṣẹ OLUWA, nitori ohun ẹ̀ru li emi o fi ọ ṣe. 11 Iwọ kiyesi eyiti emi palaṣẹ fun ọ li oni yi: kiyesi i, emi lé awọn Amori jade niwaju rẹ, ati awọn ara Kenaani, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi. 12 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nibikibi ti iwọ nlọ, ki o má ba di idẹwò fun ọ lãrin rẹ: 13 Bikoṣepe ki ẹnyin ki o wó pẹpẹ wọn, ki ẹnyin ki o fọ́ ọwọ̀n wọn, ki ẹnyin si wó ere oriṣa wọn lulẹ. 14 Nitoriti ẹnyin kò gbọdọ bọ oriṣa: nitori OLUWA, orukọ ẹniti ijẹ Ojowu, Ọlọrun ojowú li on: 15 Ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nigbati nwọn ba nṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ti nwọn si nrubọ si oriṣa wọn, ti nwọn si pè ọ ti iwọ si lọ jẹ ninu ẹbọ wọn; 16 Ki iwọ ki o má si ṣe fẹ́ ninu awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmokọnrin rẹ, ki awọn ọmọbinrin wọn ki o má ba ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ki nwọn ki o má ba mu ki awọn ọmọkunrin rẹ ki o ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn. 17 Iwọ kò gbọdọ dà ere oriṣakoriṣa kan fun ara rẹ. 18 Ajọ aiwukàra ni ki iwọ ki o ma pamọ́. Ijọ́ meje ni iwọ o jẹ àkara alaiwu, bi mo ti paṣẹ fun ọ, ni ìgba oṣù Abibu: nitoripe li oṣù Abibu ni iwọ jade kuro ni Egipti. 19 Gbogbo akọ́bi ni ti emi; ati akọ ninu gbogbo ohunọ̀sin rẹ; akọ́bi ti malu, ati ti agutan. 20 Ṣugbọn akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada: bi iwọ kò ba si rà a pada, njẹ ki iwọ ki o ṣẹ́ ẹ li ọrùn. Gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọkunrin rẹ ni ki iwọ ki o rapada. Kò si sí ẹnikan ti yio farahàn niwaju mi lọwọ ofo. 21 Ijọ́ mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ni ijọ́ keje ni ki iwọ ki o simi: ni ìgba ifunrugbìn, ati ni ìgba ikore ni ki iwọ ki o simi. 22 Iwọ o si ma kiyesi ajọ ọ̀sẹ, akọ́so eso alikama, ati ajọ ikore li opin ọdún. 23 Li ẹrinmẹta li ọdún kan ni gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa, ỌLỌRUN, Ọlọrun Israeli. 24 Nitoriti emi o lé awọn orilẹ-ède nì jade niwaju rẹ, emi o si fẹ̀ ipinlẹ rẹ: bẹ̃li ẹnikẹni ki yio fẹ́ ilẹ̀-iní rẹ, nigbati iwọ o gòke lọ lati pejọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ẹrinmẹta li ọdún kan. 25 Iwọ kò gbọdọ ta ẹ̀jẹ ẹbọ mi silẹ nibiti iwukàra wà, bẹ̃li ẹbọ ajọ irekọja kò gbọdọ kù titi di owurọ̀. 26 Akọ́so eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o mú wa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀. 27 OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ kọwe ọ̀rọ wọnyi: nitori nipa ìmọ ọ̀rọ wọnyi li emi bá iwọ ati Israeli dá majẹmu. 28 On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni. 29 O si ṣe, nigbati Mose sọkalẹ lati ori òke Sinai wá ti on ti walã ẹrí mejeji nì li ọwọ́ Mose, nigbati o sọkalẹ ti ori òke na wá, ti Mose kò mọ̀ pe awọ oju on ndán nitoriti o bá a sọ̀rọ. 30 Nigbati Aaroni ati gbogbo awọn ọmọ Israeli ri Mose, kiyesi i, awọ oju rẹ̀ ndán; nwọn si bẹ̀ru lati sunmọ ọdọ rẹ̀. 31 Mose si kọ si wọn; ati Aaroni ati gbogbo awọn ijoye inu ajọ si pada tọ̀ ọ́ wá: Mose si bá wọn sọ̀rọ. 32 Lẹhin eyinì ni gbogbo awọn ọmọ Israeli si sunmọ ọ: o si paṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA bá a sọ lori òke Sinai fun wọn. 33 Nigbati Mose si bá wọn sọ̀rọ tán, o fi iboju bò oju rẹ̀. 34 Ṣugbọn nigbati Mose ba lọ si iwaju OLUWA lati bá a sọ̀rọ, a mú iboju na kuro titi o fi jade: a si jade, a si bá awọn ọmọ Israeli sọ̀rọ aṣẹ ti a pa fun u. 35 Awọn ọmọ Israeli si ri oju Mose pe, awọ, oju rẹ̀ ndán: Mose si tun fi iboju bò oju rẹ̀, titi o fi wọle lọ bá a sọ̀rọ.

Eksodu 35

1 MOSE si pè apejọ gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Wọnyi li ọ̀rọ ti OLUWA palaṣẹ pe, ki ẹnyin ki o ṣe wọn. 2 Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ. 3 Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi. 4 Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe, 5 Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ; 6 Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ; 7 Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu; 8 Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; 9 Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. 10 Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ; 11 Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀; 12 Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na; 13 Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì; 14 Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna. 15 Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na; 16 Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀; 17 Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na; 18 Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn; 19 Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa. 20 Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si lọ kuro ni iwaju Mose. 21 Nwọn si wá, olukuluku ẹniti ọkàn rẹ́ ru ninu rẹ̀, ati olukuluku ẹniti ọkàn rẹ̀ mu u fẹ́, nwọn si mú ọrẹ OLUWA wá fun iṣẹ agọ́ ajọ na, ati fun ìsin rẹ̀ gbogbo, ati fun aṣọ mimọ́ wọnni. 22 Nwọn si wá, ati ọkunrin ati obinrin, iye awọn ti ọkàn wọn fẹ́, nwọn si mú jufù wá, ati oruka-eti, ati oruka-àmi, ati ilẹkẹ wurà, ati onirũru ohun ọṣọ́ wurà; ati olukuluku enia ti o nta ọrẹ, o ta ọrẹ wurà fun OLUWA. 23 Ati olukuluku enia lọdọ ẹniti a ri aṣọ-alaró, ati elesè àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ daradara, ati irun ewurẹ, ati awọ àgbo pupa, ati awọ seali, mú wọn wá. 24 Olukuluku ẹniti o ta ọrẹ fadakà ati idẹ, o mú ọrẹ OLUWA wá: ati olukuluku enia lati ọdọ ẹniti a ri igi ṣittimu fun iṣẹkiṣẹ ìsin na, mú u wá. 25 Ati gbogbo awọn obinrin ti iṣe ọlọgbọ́n inu, nwọn fi ọwọ́ wọn ranwu, nwọn si mú eyiti nwọn ran wá, ti alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ daradara. 26 Ati gbogbo awọn obinrin inu ẹniti o ru soke li ọgbọ́n nwọn ran irun ewurẹ. 27 Ati awọn ijoye mú okuta oniki wá, ati okuta ti a o tò, fun ẹ̀wu-efodi nì, ati fun igbàiya nì; 28 Ati olõrùn, ati oróro; fun fitila, ati fun oróro itasori, ati fun turari didùn. 29 Awọn ọmọ Israeli ta ọrẹ atinuwa fun OLUWA; olukuluku ọkunrin ati obinrin, ẹniti ọkàn wọn mu wọn fẹ́ lati mú u wá fun onirũru iṣẹ, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe lati ọwọ́ Mose wá, 30 Mose si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Wò o, OLUWA ti pè Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, li orukọ. 31 O si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, li oyé, ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà; 32 Ati lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, 33 Ati li okuta gbigbẹ́ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. 34 O si fi sinu ọkàn rẹ̀ lati ma kọni, ati on, ati Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani. 35 O si fi ọgbọ́n inu kún wọn, lati ṣe onirũru iṣẹ, ti alagbẹdẹ, ati ti ọnà, ati ti agunnà, li aṣọ-alaró, ati li elesè-àluko, li ododó, ati li ọ̀gbọ daradara, ati ti ahunṣọ, ati ti awọn ẹniti nṣe iṣẹkiṣẹ ati ti awọn ẹniti nhumọ̀ iṣẹ-ọnà.

Eksodu 36

1 BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ. 2 Mose si pè Besaleli ati Oholiabu, ati gbogbo ọkunrin ọlọgbọ́n inu, ninu ọkàn ẹniti OLUWA fi ọgbọ́n si, ani gbogbo ẹniti inu wọn ru soke lati wá si ibi iṣẹ na lati ṣe e: 3 Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀. 4 Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọgbọ́n, ti o ṣe gbogbo isẹ ibi mimọ́ na, lọ olukuluku kuro ni ibi iṣẹ rẹ̀ ti nwọn ṣe; 5 Nwọn si sọ fun Mose pe, Awọn enia múwa pupọ̀ju fun iṣẹ ìsin na, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe. 6 Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa. 7 Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju. 8 Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn. 9 Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna. 10 O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn. 11 O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji. 12 Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji. 13 O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́. 14 O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn. 15 Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna. 16 O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn. 17 O si pa ãdọta ojóbo si ìha eti ikangun aṣọ-tita na ni ibi isolù, ati ãdọta ojóbo li o si pa si eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù. 18 O si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ lati so agọ́ na lù pọ̀, ki o le ṣe ọkan. 19 O si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori eyi. 20 O si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo. 21 Gigùn apáko kan jẹ́ igbọnwọ mẹwa, ati ibú apáko kan jẹ́ igbọnwọ kan on àbọ. 22 Apáko kan ni ìtẹbọ meji, nwọn jìna si ara wọn li ọgbọgba; bẹ̃li o ṣe sara gbogbo apáko agọ́ na. 23 O si fi apáko ṣe agọ́ na; ogún apáko ni fun ìha ọtún, si ìha gusù: 24 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà li o ṣe nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ rẹ̀ meji, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ rẹ̀ meji. 25 Ati fun ìha keji agọ́ na, ti o wà ni ìha ariwa, o ṣe ogún apáko, 26 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ wọn ti fadakà; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji. 27 Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn o ṣe apáko mẹfa. 28 Apáko meji li o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha mejeji. 29 A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji. 30 Apáko mẹjọ li o wà, ihò-ìtẹbọ wọn si jẹ́ ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun ti fadakà; ìtẹbọ mejimeji li o wà nisalẹ apáko kọkan. 31 O si ṣe ọpá igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na, 32 Ati ọpá marun fun apáko ìha keji agọ́ na, ati ọpá marun fun apáko agọ́ na fun ìha ìwọ-õrùn. 33 O si ṣe ọpá ãrin o yọ jade lara apáko wọnni, lati opin ekini dé ekeji. 34 O si fi wurà bò apáko wọnni, o si fi wurà ṣe oruka wọn, lati ṣe ipò fun ọpá wọnni, o si fi wurà bò ọpá wọnni. 35 O si fi aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ṣe aṣọ-ikele: iṣẹ ọlọnà li o fi ṣe e ti on ti awọn kerubu. 36 O si ṣe opó igi ṣittimu mẹrin si i, o si fi wurà bò wọn: kọkọrọ wọn ti wurà ni, o si dà ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrin fun wọn. 37 O si ṣe aṣọ-isorọ̀ kan fun ẹnu-ọ̀na Agọ́ na, aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti iṣẹ abẹ́rẹ; 38 Ati opó rẹ̀ mararun ti on ti kọkọrọ wọn: o si fi wurà bò ọnà ori wọn, ati ọjá wọn: ṣugbọn idẹ ni ihò-ìtẹbọ wọn mararun.

Eksodu 37

1 BESALELI si fi igi ṣittimu ṣe apoti na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: 2 O si fi kìki wurà bò o ninu ati lode, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 3 O si dà oruka wurà mẹrin fun u, lati fi si igun mẹrẹrin rẹ̀; oruka meji si ìha kini rẹ̀, ati meji si ìha keji rẹ̀. 4 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá, o si fi wurà bò wọn. 5 O si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, lati ma rù apoti na 6 O si fi kìki wurà ṣe itẹ́-ãnu na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀. 7 O si ṣe kerubu wurà meji; iṣẹ lilù li o ṣe wọn, ni ìku mejeji itẹ́-ãnu na; 8 Kerubu kan ni ìku kini, ati kerubu keji ni ìku keji: lati ara itẹ́-ãnu li o ti ṣe awọn kerubu na ni ìku mejeji rẹ̀. 9 Awọn kerubu na si nà iyẹ́-apa wọn soke, nwọn si fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, nwọn si dojukọ ara wọn; itẹ́-ãnu na ni awọn kerubu kọjusi. 10 O si fi igi ṣittimu ṣe tabili kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: 11 O si fi kìki wurà bò o, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 12 O si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, o si ṣe igbáti wurà kan fun eti rẹ̀ yiká. 13 O si dà oruka wurà mẹrin fun u, o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà ni ibi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rẹ̀. 14 Labẹ igbáti na ni oruka wọnni wà, àye fun ọpá lati fi rù tabili na. 15 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn, lati ma rù tabili na. 16 O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni. 17 O si fi kìki wurà, ṣe ọpá-fitila: iṣẹ lilù li o ṣe ọpá-fitila na; ọpá rẹ̀, ati ẹka rẹ̀, ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn: 18 Ẹka mẹfa li o jade ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan rẹ̀, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na, ni ìha keji rẹ̀. 19 Ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka kan, irudi kan ati itanna; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka keji, irudi kan ati itanna: bẹ̃ni li ẹka mẹfẹfa ti o jade lara ọpá-fitila na. 20 Ati ninu ọpá-fitila na li a ṣe ago mẹrin bi itanna almondi, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀: 21 Ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, gẹgẹ bi ẹka mẹfẹfa ti o jade lara rẹ̀. 22 Irudi wọn ati ẹka wọn jẹ bakanna: gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ lilù kìki wurà kan. 23 O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni. 24 Talenti kan kìki wurà li o fi ṣe e, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀. 25 O si fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ turari: gigùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, ibú rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ kan, ìha mẹrin ọgbọgba; giga rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ meji; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀. 26 O si fi kìki wurà bò o, ati òke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀: o si ṣe igbáti wurà si i yiká. 27 O si ṣe oruka wurà meji si i nisalẹ̀ igbáti rẹ̀ na, ni ìha igun rẹ̀ meji, ìha mejeji rẹ̀, lati ṣe àye fun ọpá wọnni lati ma fi rù u. 28 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn. 29 O si ṣe oróro mimọ́ itasori nì, ati õrùn didùn kìki turari, gẹgẹ bi iṣẹ alapòlu.

Eksodu 38

1 O SI fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ ẹbọsisun: igbọnwọ marun ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ marun ni ibú rẹ̀; onìha mẹrin ọgbọgba ni; igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀. 2 O si ṣe iwo rẹ̀ si i ni igun rẹ̀ mẹrẹrin; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀: o si fi idẹ bò o. 3 O si ṣe gbogbo ohunèlo pẹpẹ na, ìkoko rẹ̀, ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo iná wọnni: gbogbo ohunèlo rẹ̀ li o fi idẹ ṣe. 4 O si ṣe àro idẹ fun pẹpẹ na ni iṣẹ àwọn nisalẹ ayiká rẹ̀, dé agbedemeji rẹ̀. 5 O si dà oruka mẹrin fun ìku mẹrẹrin àro idẹ na, li àye fun ọpá wọnni. 6 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi idẹ bò wọn. 7 O si fi ọpá wọnni sinu oruka ni ìha pẹpẹ na, lati ma fi rù u; o fi apáko ṣe pẹpẹ na li onihò ninu. 8 O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 9 O si ṣe agbalá na: ni ìha gusù li ọwọ́ ọtún aṣọ-tita agbalá na jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ọgọrun igbọnwọ: 10 Opó wọn jẹ́ ogún, ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 11 Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 12 Ati fun ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ, opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 13 Ati fun ìha ìla-õrùn, si ìha ìla-õrùn ãdọta igbọnwọ. 14 Aṣọ-tita apakan jẹ́ igbọnwọ mẹdogun; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta. 15 Ati fun apa keji: li apa ihin ati li apa ọhún ẹnu-ọ̀na agbalá na, li aṣọ-tita onigbọnwọ mẹdogun wà; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta. 16 Gbogbo aṣọ-tita agbalá na yiká jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 17 Ati ihò-ìtẹbọ fun opó wọnni jẹ́ idẹ; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà; ati ibori ori wọn jẹ́ fadakà; ati gbogbo opó agbalá na li a fi fadakà gbà li ọjá. 18 Ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na jẹ́ iṣẹ abẹ́rẹ, aṣọ-alaró, ati elesè-aluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ: ogún igbọnwọ si ni gigùn rẹ̀, ati giga ni ibò rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun, o bá aṣọ-tita agbalá wọnni ṣedede. 19 Opó wọn si jẹ́ mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ, mẹrin; kọkọrọ wọn jẹ́ fadakà, ati ibori ori wọn ati ọjá wọn jẹ́ fadakà. 20 Ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati ti agbalá rẹ̀ yiká jẹ́ idẹ. 21 Eyi ni iye agọ́ na, agọ́ ẹrí nì, bi a ti kà wọn, gẹgẹ bi ofin Mose, fun ìrin awọn ọmọ Lefi, lati ọwọ́ Itamari wá, ọmọ Aaroni alufa. 22 Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, si ṣe ohun gbogbo ti OLUWA paṣẹ fun Mose. 23 Ati Oholiabu pẹlu rẹ̀, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, alagbẹdẹ, ati ọlọgbọ́n ọlọnà, alaró ati ahunṣọ alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara. 24 Gbogbo wurà ti a lò si iṣẹ na, ni onirũru iṣẹ ibi mimọ́ nì, ani wurà ọrẹ nì, o jẹ́ talenti mọkandilọgbọ̀n, ati ẹgbẹrin ṣekeli o din ãdọrin, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́. 25 Ati fadakà awọn ẹniti a kà ninu ijọ-enia jẹ́ ọgọrun talenti, ati ṣekeli ojidilẹgbẹsan o le mẹdogun, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́: 26 Abọ ṣekeli kan li ori ọkunrin kọkan, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́, lori ori olukuluku ti o kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ le ẹgbẹtadilogun o le ãdọjọ enia. 27 Ati ninu ọgọrun talenti fadakà na li a ti dà ihò-ìtẹbọ wọnni ti ibi mimọ́, ati ihò-ìtẹbọ ti aṣọ-ikele na, ọgọrun ihò-ìtẹbọ ninu ọgọrun talenti na, talenti ka fun ihò-ìtẹbọ kan. 28 Ati ninu ojidilẹgbẹsan ṣekeli o le mẹdogun, o mú ṣe kọkọrọ fun ọwọ̀n wọnni, o si fi i bò ori wọn, o si fi i ṣe ọjá wọn. 29 Ati idẹ ọrẹ na jẹ́ ãdọrin talenti, ati egbejila ṣekeli. 30 On li o si fi ṣe ihò-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ati pẹpẹ idẹ na, ati àro idẹ sara rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na, 31 Ati ihò-ìtẹbọ agbalá, na yikà, ati ìho-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agbalá, ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati gbogbo ekàn agbalà na yikà.

Eksodu 39

1 NWỌN si fi ninu aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, dá aṣọ ìsin, lati ma fi sìn ni ibi mimọ́, nwọn si dá aṣọ mimọ́ ti iṣe fun Aaroni; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 2 O si ṣe ẹ̀wu-efodi na ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 3 Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì. 4 Nwọn ṣe aṣọ ejika si i, lati so o lù: li eti mejeji li a so o lù. 5 Ati onirũru-ọnà ọjá ti o wà lara rẹ̀, lati fi dì i o jẹ́ ọkanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, aṣọ-alaró, elesè-àluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 6 Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si. 7 O si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi na, li okuta, iranti fun awọn ọmọ Israeli: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 8 O si fi iṣẹ ọlọnà ṣiṣẹ igbàiya na, bi iṣẹ ẹ̀wu-efodi nì; ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododo, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. 9 Oniha mẹrin ọgbọgba ni; nwọn ṣe igbàiya na ni iṣẹpo meji: ika kan ni gigùn rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀, o jẹ́ iṣẹpo meji. 10 Nwọn si tò ẹsẹ̀ okuta mẹrin si i: ẹsẹ̀ ekini ni sardiu, ati topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini. 11 Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi. 12 Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu. 13 Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, oniki, ati jasperi: a si tò wọn si oju-ìde wurà ni titò wọn. 14 Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila. 15 Nwọn si ṣe ẹ̀wọn iṣẹ-ọnà-lilọ kìki wurà si igbàiya na. 16 Nwọn si ṣe oju-ìde wurà meji, ati oruka wurà meji; nwọn si fi oruka mejeji si eti igbàiya na mejeji. 17 Nwọn si fi ẹ̀wọn wurà iṣẹ-ọnà-lilọ mejeji bọ̀ inu oruka wọnni, ni eti igbàiya na. 18 Ati eti mejeji ti ẹ̀wọn iṣẹ-lilọ mejeji nì ni nwọn fi mọ́ inu oju-ìde mejeji, nwọn si fi wọn sara okùn ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀. 19 Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si eti mejeji igbàiya na, si eti rẹ̀ ti o wà, ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inu. 20 Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si ìha mejeji ẹ̀wu-efodi na nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ki o kọjusi isolù rẹ̀, loke ọjá ẹ̀wu-efodi na. 21 Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 22 O si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni iṣẹ wiwun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ-aláró. 23 Oju-ọrùn si wà li agbedemeji aṣọ-igunwa na, o dabi oju-ẹ̀wu ogun, pẹlu ọjá yi oju na ká, ki o máṣe ya. 24 Nwọn si ṣe pomegranate aṣọ: alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ si iṣẹti aṣọ-igunwa na. 25 Nwọn si ṣe ṣaworo kìki wurà, nwọn si fi ṣaworo na si alafo pomegranate wọnni si eti iṣẹti aṣọ igunwa na, yiká li alafo pomegranate wọnni; 26 Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 27 Nwọn si ṣe ẹ̀wu ọ̀gbọ daradara ti iṣẹ híhun fun Aaroni, ati fun awọn ọmo rẹ̀, 28 Ati fila ọṣọ́ ọ̀gbọ daradara, ati fila ọ̀gbọ didara, ati ṣòkoto ọ̀gbọ olokún wiwẹ, 29 Ati ọjá ọ̀gbọ olokùn wiwẹ́, ati ti aṣọ-alaró, ti elesè-àluko, ati ti ododo, oniṣẹ abẹ́rẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 30 Nwọn si ṣe awo adé mimọ́ na ni kìki wurà, nwọn si kọwe si i, ikọwe bi fifin èdidi-àmi, MIMỌ SI OLUWA. 31 Nwọn si dì ọjá àwọn alaró mọ́ ọ, lati fi dì i loke sara fila na; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 32 Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ agọ́ ti agọ́ ajọ na pari: awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA palaṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe. 33 Nwọn si mú agọ́ na tọ̀ Mose wá, agọ́ na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ikọ́ rẹ̀, apáko rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ati ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ wọnni; 34 Ati ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati ibori awọ seali, ati ikele aṣọ-tita. 35 Apoti ẹrí nì, ati ọpá rẹ̀ wọnni, ati itẹ́-ãnu nì; 36 Tabili na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati àkara ifihàn; 37 Ọpá-fitila mimọ́, pẹlu fitila rẹ̀ wọnni, fitila ti a tò li ẹsẹ̀-ẹsẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati oróro titanna; 38 Ati pẹpẹ wurà, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na; 39 Pẹpẹ idẹ, ati oju-àro-àwọn idẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, agbada na ati ẹsẹ̀ rẹ̀; 40 Aṣọ-tita agbalá na, ọwọ̀n rẹ̀ ati ihò-ìtẹbọ̀ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na, okùn rẹ̀, ati ekàn rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo ìsin agọ́ na, ani agọ́ ajọ; 41 Aṣọ ìsin lati ma fi sìn ninu ibi mimọ́, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa. 42 Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na. 43 Mose si bojuwò gbogbo iṣẹ na, si kiyesi i, nwọn si ṣe e bi OLUWA ti palaṣẹ, bẹ̃ gẹgẹ ni nwọn ṣe e; Mose si sure fun wọn.

Eksodu 40

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Li ọjọ́ kini oṣù kini ni ki iwọ ki o gbé ibugbé agọ́ na ró. 3 Iwọ o si fi apoti ẹrí nì sinu rẹ̀, iwọ o si ta aṣọ-ikele ni bò apoti na. 4 Iwọ o si gbé tabili wọle, ki o si tò ohun wọnni ti o ni itò si ori rẹ̀; iwọ o si mú ọpá-fitila wọle, iwọ o si tò fitila rẹ̀ wọnni lori rẹ̀. 5 Iwọ o si fi pẹpẹ wurà ti turari nì si iwaju apoti ẹrí, iwọ o si fi aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na sara agọ́ na. 6 Iwọ o si fi pẹpẹ ẹbọsisun nì si iwaju ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ. 7 Iwọ o si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀. 8 Iwọ o si fà agbalá na yiká, iwọ o si ta aṣọ-isorọ̀ si ẹnu-ọ̀na agbalá na. 9 Iwọ o si mù oróro itasori nì, iwọ o si ta a sara agọ́ na, ati sara ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀: yio si jẹ́ mimọ́. 10 Iwọ o si ta oróro sara pẹpẹ ẹbọsisun, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, iwọ o si yà pẹpẹ na simimọ́: yio si ma jẹ́ pẹpẹ ti o mọ́ julọ. 11 Iwọ o si ta oróro sara agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́. 12 Iwọ o si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn. 13 Iwọ o si fi aṣọ mimọ́ wọnni wọ̀ Aaroni; iwọ o si ta oróro si i li ori, iwọ o si yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi. 14 Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá, iwọ o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn: 15 Iwọ o si ta oróro si wọn li ori, bi iwọ ti ta si baba wọn li ori, ki nwọn ko le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi: nitoriti itasori wọn yio jẹ́ iṣẹ-alufa lailai nitõtọ, lati irandiran wọn. 16 Bẹ̃ni Mose ṣe: gẹgẹ bi eyiti OLUWA palaṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe. 17 O si ṣe li oṣù kini li ọdún keji ni ijọ́ kini oṣù na, ni a gbé agọ́ na ró. 18 Mose si gbé agọ́ na ró, o si de ihò-ìtẹbọ rẹ̀, o si tò apáko rẹ̀, o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ, o si gbé ọwọ̀n rẹ̀ ró. 19 O si nà aṣọ agọ́ na sori agọ́, o si fi ibori agọ́ na bò o li ori; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 20 O si mú, o si fi ẹrí nì sinu apoti na, o si fi ọpá wọnni sara apoti na, o si fi itẹ́-ãnu nì si oke lori apoti na: 21 O si gbé apoti na wá sinu agọ́, o si ta aṣọ-ikele, o si ta a bò apoti ẹrí; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 22 O si fi tabili nì sinu agọ́ ajọ, ni ìha ariwa agọ́ na, lẹhin ode aṣọ-ikele nì. 23 O si tò àkara na lẹ̀sẹsẹ daradara lori rẹ̀ niwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 24 O si fi ọpá-fitila nì sinu agọ́ ajọ, ki o kọjusi tabili nì ni ìha gusù agọ na. 25 O si tàn fitila wọnni siwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 26 O si fi pẹpẹ wurà nì sinu agọ́ ajọ niwaju aṣọ-ikele nì: 27 O si fi turari didùn joná lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 28 O si ta aṣọ-isorọ̀ nì si ẹnu-ọ̀na agọ́ na. 29 O si fi pẹpẹ ẹbọsisun si ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ, o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 30 O si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, o si pọn omi si i, lati ma fi wẹ̀. 31 Ati Mose ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wẹ̀ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn ninu rẹ̀. 32 Nigbati nwọn ba lọ sinu agọ́ ajọ, ati nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ na, nwọn a wẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 33 O si fà agbalá na yi agọ́ ati pẹpẹ na ká, o si ta aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na. Bẹ̃ni Mose pari iṣẹ na. 34 Nigbana li awọsanma bò agọ́ ajọ, ogo OLUWA si kún inu agọ́ na. 35 Mose kò si le wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nitoriti awọsanma wà lori rẹ̀, ogo OLUWA si kun inu agọ́ na. 36 Nigbati a si fà awọsanma na soke, kuro lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a ma dide rìn lọ ni ìrin wọn gbogbo: 37 Ṣugbọn bi a kò fà awọsanma na soke, njẹ nwọn kò ni idide rìn titi ọjọ-kọjọ́ ti o ba fà soke. 38 Nitoriti awọsanma OLUWA wà lori agọ́ na li ọsán, iná si wà ninu awọsanma na li oru, li oju gbogbo ile Israeli, ni gbogbo ìrin wọn.

Lefitiku 1

Àwọn Ẹbọ Tí A Sun Lódidi

1 OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikan ninu nyin ba mú ọrẹ-ẹbọ wá fun OLUWA, ki ẹnyin ki o mú ọrẹ-ẹbọ nyin wá ninu ohunọ̀sin, ani ti inu ọwọ́-ẹran, ati ti agbo-ẹran. 3 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA. 4 Ki o si fi ọwọ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si di itẹwọgbà fun u lati ṣètutu fun u. 5 Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, yio si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 6 Ki o si bó ẹbọ sisun na; ki o si kun u. 7 Awọn ọmọ Aaroni alufa ni yio si fi iná sori pẹpẹ na, nwọn o si tò igi lori iná na: 8 Awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si tò ninu rẹ̀, ani ori ati ọrá wọn sori igi ti mbẹ lori iná, ti mbẹ lori pẹpẹ: 9 Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 10 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ti agbo-ẹran, eyinì ni ti agutan, tabi ti ewurẹ, fun ẹbọ sisun; akọ ni ki o múwa alailabùku. 11 Ki o si pa a niwaju OLUWA li ẹba pẹpẹ ni ìha ariwa: ati awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si bù ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 12 Ki o si kun u, ori rẹ̀ ati ọrá rẹ̀: alufa na yio si tò wọn sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ: 13 Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 14 Bi o ba si ṣepe ti ẹiyẹ ni ẹbọ sisun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA, njẹ ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá ninu àdaba, tabi ninu ọmọ ẹiyẹle. 15 Ki alufa na ki o si mú u wá si pẹpẹ na, ki o si mi i li ọrùn, ki o si sun u lori pẹpẹ na; ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ki o si ro si ẹba pẹpẹ na. 16 Ki o si fà ajẹsi rẹ̀ já pẹlu ẽri rẹ̀, ki o si kó o lọ si ẹba pẹpẹ na ni ìha ìlà-õrùn, lori ibi ẽru nì: 17 Ki o si là a ti on ti iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki yio pín i ni meji jalẹ: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ na, lori igi na ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Lefitiku 2

Ẹbọ Ohun Jíjẹ

1 NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀. 2 Ki o si mú u tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni wá: ki alufa si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun na, ati ninu oróro na, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, lati ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA: 3 Iyokù ti ẹbọ ohunjijẹ na, a si jẹ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ lati inu ẹbọ OLUWA ni ti a fi iná ṣe. 4 Bi iwọ ba si mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ wá, ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si. 5 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ohunjijẹ, ti a ṣe ninu awopẹtẹ, ki o jẹ́ ti iyẹfun didara alaiwu, ti a fi òróró pò. 6 Ki iwọ ki o si dá a kelekele, ki o si dà oróro sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni. 7 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ ba ṣe ẹbọ ohunjijẹ, ti a yan ninu apẹ, iyẹfun didara ni ki a fi ṣe e pẹlu oróro. 8 Ki iwọ ki o si mú ẹbọ ohunjijẹ na wá, ti a fi nkan wọnyi ṣe fun OLUWA: on o si mú u tọ̀ alufa na wá, ki on ki o si mú u wá sori pẹpẹ nì. 9 Alufa yio si mú ẹbọ-iranti ninu ohunjijẹ na, yio si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 10 Eyiti o si kù ninu ẹbọ ohunjijẹ, ki o jẹ́ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni, ọrẹ-ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe. 11 A kò gbọdọ fi iwukàra ṣe gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti ẹnyin o mú tọ̀ OLUWA wá: nitori ẹnyin kò gbọdọ sun iwukàra, tabi: oyinkoyin, ninu ọrẹ-ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe. 12 Bi ọrẹ-ẹbọ akọ́so, ẹnyin le mú wọn wá fun OLUWA: ṣugbọn a ki yio sun wọn lori pẹpẹ fun õrùn didùn. 13 Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o má sí ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ si. 14 Bi iwọ ba si mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá fun OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà daradara ti a yan lori iná wá fun ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ, ọkà gigún, ti ṣiri tutù. 15 Ki iwọ ki o si fi oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni. 16 Ki alufa ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀, apakan ninu ọkà gigún rẹ̀, ati apakan ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

Lefitiku 3

Ẹbọ Alaafia

1 BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku. 2 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká. 3 Ki o si mú ninu ẹbọ alafia nì wá, ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na. 4 Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ́ lara wọn, ti mbẹ li ẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro. 5 Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA. 6 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ọrẹ-ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agbo-ẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku. 7 Bi o ba mu ọdọ-agutan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA: 8 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 9 Ki o si múwa ninu ẹbọ alafia nì, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀ ti o lọrá, on ni ki o mú kuro sunmọ egungun ẹhin; ati ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, 10 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro. 11 Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni. 12 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA: 13 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 14 Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, 15 Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro. 16 Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe fun õrùn didùn ni: ti OLUWA ni gbogbo ọrá. 17 Ìlana titilai ni fun irandiran nyin, ni gbogbo ibugbé nyin, pe ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ọrá tabi ẹ̀jẹ.

Lefitiku 4

Ẹbọ fún Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Eniyan Bá Ṣèèṣì Dá

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkàn kan ba fi aimọ̀ sẹ̀ si ọkan ninu ofin OLUWA, li ohun ti kò yẹ ni ṣiṣe, ti o si ṣẹ̀ si ọkan ninu wọn: 3 Bi alufa ti a fi oróro yàn ba ṣẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ awọn enia; nigbana ni ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan alailabùku fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti ṣẹ̀. 4 Ki o si mú akọmalu na wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA; ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori akọmalu na, ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA. 5 Ki alufa na ti a fi oróro yàn, ki o bù ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si mú u wá si agọ́ ajọ: 6 Ki alufa na ki o tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ na wọ́n nkan nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele ibi mimọ́. 7 Ki alufa ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ turari didùn niwaju OLUWA, eyiti mbẹ ninu agọ́ ajọ; ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ akọmalu nì si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 8 Ki o si mú gbogbo ọrá akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ kuro lara rẹ̀; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na, 9 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro, 10 Bi a ti mú u kuro lara akọmalu ẹbọ-ọrẹ ẹbọ alafia: ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ ẹbọsisun. 11 Ati awọ akọmalu na, ati gbogbo ẹran rẹ̀, pẹlu ori rẹ̀, ati pẹlu itan rẹ̀, ati ifun rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, 12 Ani gbogbo akọmalu na ni ki o mú jade lọ sẹhin ibudó si ibi mimọ́ kan, ni ibi ti a ndà ẽru si, ki o si fi iná sun u lori igi: ni ibi ti a ndà ẽru si ni ki a sun u. 13 Bi gbogbo ijọ enia Israeli ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, ti ohun na si pamọ́ li oju ijọ, ti nwọn si ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA, ti a ki ba ṣe, ti nwọn si jẹbi; 14 Nigbati ẹ̀ṣẹ ti nwọn ba ti ṣẹ̀ si i, ba di mimọ̀, nigbana ni ki ijọ enia ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá nitori ẹ̀ṣẹ na, ki nwọn ki o si mú u wá siwaju agọ́ ajọ. 15 Ki awọn àgbagba ijọ enia ki o fi ọwọ́ wọn lé ori akọmalu na niwaju OLUWA: ki a si pa akọmalu na niwaju OLUWA. 16 Ki alufa ti a fi oróro yàn ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na wá si agọ́ ajọ: 17 Ki alufa na ki o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si wọ́n ọ nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele. 18 Ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ti mbẹ ninu agọ́ ajọ, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 19 Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ lara rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ. 20 Ki o si fi akọmalu na ṣe; bi o ti fi akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ṣe, bẹ̃ni ki o si fi eyi ṣe: ki alufa na ki o si ṣètutu fun wọn, a o si dari rẹ̀ jì wọn. 21 Ki o si gbé akọmalu na jade lọ sẹhin ibudó, ki o si sun u bi o ti sun akọmalu iṣaju: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni fun ijọ enia. 22 Nigbati ijoye kan ba ṣẹ̀, ti o si fi aimọ̀ rú ọkan ninu ofin OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ti a ki ba rú, ti o si jẹbi; 23 Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ninu eyiti o ti ṣẹ̀, ba di mímọ̀ fun u; ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, akọ alailabùku: 24 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ewurẹ na, ki o si pa a ni ibiti nwọn gbé npa ẹbọ sisun niwaju OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 25 Ki alufa na ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà ẹ̀jẹ si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun. 26 Ki o si sun gbogbo ọrá rẹ̀ li ori pẹpẹ, bi ti ọrá ẹbọ alafia: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. 27 Bi ọkan ninu awọn enia ilẹ na ba fi aimọ̀ sẹ̀, nigbati o ba ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA ti a ki ba ṣe, ti o si jẹbi; 28 Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀, ba di mimọ̀ fun u, nigbana ni ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, abo alailabùku, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀. 29 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ni ibi ẹbọsisun. 30 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ. 31 Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn si OLUWA; ki alufa na ki o si ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i. 32 Bi o ba si mú ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si mú u wá, abo alailabùku. 33 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa a fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni ibi ti nwọn gbé npa ẹbọ sisun. 34 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ: 35 Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá ọdọ-agutan kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.

Lefitiku 5

Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Ó Nílò Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀ṣẹ̀

1 BI ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o si gbọ́ ohùn ibura, ti o si ṣe ẹlẹri, bi on ba ri tabi bi on ba mọ̀, ti kò ba wi, njẹ ki o rù aiṣedede rẹ̀. 2 Tabi bi ẹnikan ba farakàn ohun alaimọ́ kan, iba ṣe okú ẹranko alaimọ́, tabi okú ẹranọ̀sin alaimọ́, tabi okú ohun ti nrakò alaimọ́, ti o ba si pamọ́ fun u, on pẹlu yio si ṣe alaimọ́, yio si jẹbi: 3 Tabi bi o ba farakàn ohun aimọ́ ti enia, ohunkohun aimọ́ ti o wù ki o ṣe ti a fi sọ enia di elẽri, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi: 4 Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi: 5 Yio si ṣe, nigbati o ba jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi, ki o jẹwọ pe on ti ṣẹ̀ li ohun na. 6 Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 7 Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun. 8 Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, ẹniti yio tète rubọ eyiti iṣe ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti yio si mi i li ọrùn, ṣugbọn ki yio pín i meji: 9 Ki o si fi ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì wọ́n ìha pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ iyokù ni ki a ro si isalẹ pẹpẹ na: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 10 Ki o si ru ekeji li ẹbọ sisun, gẹgẹ bi ìlana na: ki alufa ki o si ṣètutu fun u, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. 11 Ṣugbọn bi on kò ba le mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá, njẹ ki ẹniti o ṣẹ̀ na ki o mú idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun daradara wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki o máṣe fi oróro si i, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sori rẹ̀: nitoripe ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 12 Nigbana ni ki o mú u tọ̀ alufa wá, ki alufa ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ani ẹbọ-iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ na, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 13 Ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀ li ọkan ninu wọnyi, a o si dari rẹ̀ jì i: iyokù si jẹ́ ti alufa, bi ẹbọ ohunjijẹ.

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

14 OLUWA si sọ fun Mose pe, 15 Bi ẹnikan ba ṣìṣe, ti o ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀ ninu ohun mimọ́ OLUWA; nigbana ni ki o múwa fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran wá, ni idiyele rẹ nipa ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 16 Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i. 17 Bi ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o ba si ṣe ọkan ninu nkan wọnyi, eyiti ofin OLUWA kọ̀ lati ṣe; bi kò tilẹ mọ̀, ṣugbọn o jẹbi, yio si rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18 Ki o si mú àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá ni idiyele rẹ, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori aimọ̀ rẹ̀ ninu eyiti o ṣìṣe ti kò si mọ̀, a o si dari rẹ̀ jì i. 19 Ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni: nitõtọ li o dẹ̀ṣẹ si OLUWA.

Lefitiku 6

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀, ti o dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ti o si sẹ́ fun ẹnikeji rẹ̀, li ohun ti o fi fun u pamọ́, tabi li ohun ti a fi dógo, tabi ohun ti a fi agbara gbà, tabi ti o rẹ ẹnikeji rẹ̀ jẹ; 3 Tabi ti o ri ohun ti o nù he, ti o si ṣeké nitori rẹ̀, ti o si bura eké; li ọkan ninu gbogbo ohun ti enia ṣe, ti o ṣẹ̀ ninu rẹ̀: 4 Yio si ṣe, bi o ba ti ṣẹ̀, ti o si jẹbi, ki o si mú ohun ti o fi agbara gbà pada, tabi ohun ti o fi irẹjẹ ní, tabi ohun ti a fi fun u pamọ́, tabi ohun ti o nù ti o rihe. 5 Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 6 Ki o si mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wá fun OLUWA, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá, ni idiyele rẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: 7 Alufa yio si ṣètutu fun u niwaju OLUWA, a o si dari rẹ̀ jì; nitori ohunkohun ninu gbogbo ohun eyiti o ti ṣe ti o si jẹbi ninu rẹ̀.

Ẹbọ Sísun Lódidi

8 OLUWA si sọ fun Mose pe, 9 Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀. 10 Ki alufa ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ rẹ̀ wọ̀, ati ṣòkoto ọ̀gbọ rẹ̀ nì ki o fi si ara rẹ̀, ki o si kó ẽru ti iná jọ, ti on ti ẹbọ sisun lori pẹpẹ, ki o si fi i si ìha pẹpẹ. 11 Ki o si bọ́ ẹ̀wu rẹ̀ silẹ, ki o si mú ẹ̀wu miran wọ̀, ki o si gbé ẽru wọnni jade lọ sẹhin ibudó si ibi kan ti o mọ́. 12 Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀. 13 Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai.

Ẹbọ Ohun Jíjẹ

14 Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ. 15 Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA. 16 Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ. 17 Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi. 18 Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́. 19 OLUWA si sọ fun Mose pe, 20 Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ. 21 Ninu awopẹtẹ ni ki a fi oróro ṣe e; nigbati a ba si bọ̀ ọ, ki iwọ ki o si mú u wọ̀ ile: ati ìṣu yiyan ẹbọ ohunjijẹ na ni ki iwọ ki o fi rubọ õrùn didùn si OLUWA. 22 Ati alufa ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi oróro yàn ni ipò rẹ̀ ni ki o ru u: aṣẹ titilai ni fun OLUWA, sisun ni ki a sun u patapata. 23 Nitori gbogbo ẹbọ ohunjijẹ alufa, sisun ni ki a sun u patapata: a kò gbọdọ jẹ ẹ.

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀ṣẹ̀

24 OLUWA si sọ fun Mose pe, 25 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ni ibi ti a gbé pa ẹbọ sisun, ni ki a si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ niwaju OLUWA: mimọ́ julọ ni. 26 Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ. 27 Ohunkohun ti o ba kàn ẹran rẹ̀ yio di mimọ́: nigbati ẹ̀jẹ rẹ̀ ba si ta sara aṣọ kan, ki iwọ ki o si fọ̀ eyiti o ta si na ni ibi mimọ́ kan. 28 Ṣugbọn ohunèlo àmọ, ninu eyiti a gbé bọ̀ ọ on ni ki a fọ́; bi a ba si bọ̀ ọ ninu ìkoko idẹ, ki a si fọ̀ ọ, ki a si ṣìn i ninu omi. 29 Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: mimọ́ julọ ni. 30 Kò si sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ kan, ẹ̀jẹ eyiti a múwa sinu agọ́ ajọ, lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ti a gbọdọ jẹ: sisun ni ki a sun u ninu iná.

Lefitiku 7

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

1 EYI si li ofin ẹbọ ẹbi: mimọ́ julọ ni. 2 Ni ibi ti nwọn gbé pa ẹbọ sisun ni ki nwọn ki o pa ẹbọ ẹbi: ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ yiká. 3 Ki o si fi gbogbo ọrá inu rẹ̀ rubọ; ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati ọrá ti o bò ifun lori, 4 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro: 5 Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹbi ni. 6 Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni. 7 Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i. 8 Ati alufa ti nru ẹbọ sisun ẹnikẹni, ani alufa na ni yio ní awọ ẹran ẹbọ sisun, ti o ru fun ara rẹ̀. 9 Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àro, ati gbogbo eyiti a yan ninu apẹ, ati ninu awopẹtẹ, ni ki o jẹ́ ti alufa ti o ru u. 10 Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò, ati gbigbẹ, ni ki gbogbo awọn ọmọ Aaroni ki o ní, ẹnikan bi ẹnikeji rẹ̀.

Ẹbọ Alaafia

11 Eyi si ni ofin ẹbọ alafia, ti on o ru si OLUWA. 12 Bi o ba mú u wá fun idupẹ́, njẹ ki o mú adidùn àkara alaiwu wá ti a fi oróro pò, pẹlu ẹbọ ọpẹ́ rẹ̀, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati adidùn àkara iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, ti a din. 13 Pẹlu adidùn àkara wiwu ki o mú ọrẹ-ẹbọ pẹlu ẹbọ alafia rẹ̀ wa fun idupẹ́. 14 Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia. 15 Ati ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ fun idupẹ́, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti a fi rubọ; ki o máṣe kù ninu rẹ̀ silẹ titi di owurọ̀. 16 Ṣugbọn bi ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ba ṣe ti ẹjẹ́, tabi ọrẹ-ẹbọ atinuwá, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti o ru ẹbọ rẹ̀: ati ni ijọ́ keji ni ki a jẹ iyokù rẹ̀ pẹlu: 17 Ṣugbọn iyokù ninu ẹran ẹbọ na ni ijọ́ kẹta ni ki a fi iná sun. 18 Bi a ba si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, ki yio dà, bẹ̃li a ki yio kà a si fun ẹniti o ru u: irira ni yio jasi, ọkàn ti o ba si jẹ ẹ yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 19 Ẹran ti o ba si kàn ohun aimọ́ kan, a kò gbọdọ jẹ ẹ; sisun ni ki a fi iná sun u. Ṣugbọn ẹran na ni, gbogbo ẹniti o mọ́ ni ki o jẹ ninu rẹ̀. 20 Ṣugbọn ọkàn na ti o ba jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ti on ti ohun aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 21 Pẹlupẹlu ọkàn na ti o ba fọwọkàn ohun aimọ́ kan, bi aimọ́ enia, tabi ẹranko alaimọ́, tabi ohun irira elẽri, ti o si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 22 OLUWA si sọ fun Mose pe, 23 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ọrákọra akọmalu, tabi ti agutan, tabi ti ewurẹ. 24 Ati ọrá ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, ati ọrá eyiti ẹranko fàya, on ni ki a ma lò ni ilò miran: ṣugbọn ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ. 25 Nitoripe ẹnikẹni ti o ba jẹ ọrá ẹran, ninu eyiti enia mú rubọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ani ọkàn ti o ba jẹ ẹ on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 26 Pẹlupẹlu ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, iba ṣe ti ẹiyẹ tabi ti ẹran, ninu ibugbé nyin gbogbo. 27 Ọkànkọkàn ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 28 OLUWA si sọ fun Mose pe, 29 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹniti o ba ru ẹbọ alafia rẹ̀ si OLUWA, ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ tọ̀ OLUWA wá ninu ẹbọ alafia rẹ̀: 30 Ọwọ́ on tikara rẹ̀ ni ki o fi mú ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe wá; ọrá pẹlu igẹ̀ rẹ̀, on ni ki o múwa, ki a le fì igẹ̀ na li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 31 Ki alufa na ki o sun ọrá na lori pẹpẹ: ṣugbọn ki igẹ̀ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀. 32 Itan ọtún ni ki ẹnyin ki o fi fun alufa, fun ẹbọ agbesọsoke ninu ẹbọ alafia nyin. 33 Ninu awọn ọmọ Aaroni ẹniti o rubọ ẹ̀jẹ ẹbọ alafia, ati ọrá, ni ki o ní itan ọtun fun ipín tirẹ̀. 34 Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli. 35 Eyi ni ipín Aaroni, ati ìpín awọn ọmọ rẹ̀, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, li ọjọ́ na ti o mú wọn wá lati ṣe alufa OLUWA; 36 Ti OLUWA palaṣẹ lati fi fun wọn lati inu awọn ọmọ Israeli, li ọjọ́ ti o fi oróro yàn wọn. Ìlana lailai ni iraniran wọn. 37 Eyi li ofin ẹbọ sisun, ti ẹbọ ohunjijẹ, ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ti ẹbọ ẹbi, ati ti ìyasimimọ́, ati ti ẹbọ alafia; 38 Ti OLUWA palaṣẹ fun Mose li òke Sinai, li ọjọ́ ti o paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá fun OLUWA ni ijù Sinai.

Lefitiku 8

Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan; 3 Ki iwọ ki o si pè gbogbo ijọ enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 4 Mose si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u; a si pe awọn enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 5 Mose si wi fun ijọ enia pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ lati ṣe. 6 Mose si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá, o si fi omi wẹ̀ wọn. 7 O si wọ̀ ọ li ẹ̀wu, o si fi amure dì i, o si fi aṣọ igunwa wọ̀ ọ, o si wọ̀ ọ li ẹ̀wu-efodi, o si fi onirũru-ọ̀na ọjá ẹ̀wu-efodi dì i, o si fi gbà a li ọjá. 8 O si dì igbàiya mọ́ ọ; o si fi Urimu ati Tummimu sinu igbàiya na. 9 O si fi fila dé e li ori; ati lara fila na pẹlu, ani niwaju rẹ̀, li o fi awo wurà na si, adé mimọ́ nì; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 10 Mose si mú oróro itasori, o si ta a sara agọ́, ati sara ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, o si yà wọn simimọ́. 11 O si mú ninu rẹ̀ fi wọ́n ori pẹpẹ nigba meje, o si ta a sara pẹpẹ na, ati si gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, lati yà wọn simimọ́. 12 O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́. 13 Mose si mú awọn ọmọ Aaroni wá, o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn, o si fi amure di wọn, o si fi fila dé wọn li ori; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 14 O si mú akọmalu wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ fọwọ́ wọn lé ori akọmalu na fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 15 O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u. 16 O si mú gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, Mose si sun u lori pẹpẹ. 17 Ṣugbọn akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, on li o fi iná sun lẹhin ibudó; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 18 O si mú àgbo ẹbọ sisun wá: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na. 19 O si pa a: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká. 20 O si kun àgbo na; Mose si sun ori rẹ̀, ati ara rẹ̀, ati ọrá na. 21 O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 22 O si mú àgbo keji wá, àgbo ìyasimimọ́: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na. 23 O si pa a; Mose si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀. 24 O si mú awọn ọmọ Aaroni wá, Mose si tọ́ ninu ẹ̀jẹ na si eti ọtún wọn, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká. 25 O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún: 26 Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na: 27 O si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni li ọwọ́, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀, o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 28 Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 29 Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 30 Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 31 Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ. 32 Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun. 33 Ki ẹnyin ki o máṣe jade si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ni ijọ́ meje, titi ọjọ́ ìyasimimọ́ nyin yio fi pé; nitori ijọ́ meje ni a o fi yà nyin simimọ́. 34 Bi o ti ṣe li oni yi, bẹ̃li OLUWA fi aṣẹ lelẹ lati ṣe, lati ṣètutu fun nyin. 35 Nitorina ni ki ẹnyin ki o joko nibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, li ọsán ati li oru ni ijọ́ meje, ki ẹnyin ki o si ma pa aṣẹ OLUWA mọ́, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi. 36 Bẹ̃li Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo ti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ lati ọwọ́ Mose wá.

Lefitiku 9

Aaroni Rúbọ sí OLUWA

1 O si ṣe ni ijọ́ kẹjọ, ni Mose pè Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn àgba Israeli; 2 O si wi fun Aaroni pe, Mú ọmọ akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùku fun ẹbọ sisun, ki o fi wọn rubọ niwaju OLUWA. 3 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ mú obukọ kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ati ọmọ malu kan, ati ọdọ-agutan kan, mejeji ọlọdún kan, alailabùku, fun ẹbọ sisun; 4 Ati akọmalu kan ati àgbo kan fun ẹbọ alafia, lati fi ru ẹbọ niwaju OLUWA; ati ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò: nitoripe li oni li OLUWA yio farahàn nyin. 5 Nwọn si mú ohun ti Mose filelẹ li aṣẹ́ wá siwaju agọ́ ajọ: gbogbo ijọ si sunmọtosi nwọn si duro niwaju OLUWA. 6 Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA filelẹ li aṣẹ, ki ẹnyin ki o ṣe: ogo OLUWA yio si farahàn nyin. 7 Mose si sọ fun Aaroni pe, Sunmọ pẹpẹ, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati ẹbọ sisun rẹ, ki o si ṣètutu fun ara rẹ, ati fun awọn enia: ki o si ru ọrẹ-ẹbọ awọn enia, ki o si ṣètutu fun wọn; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. 8 Aaroni si sunmọ pẹpẹ, o si pa ọmọ malu ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikalarẹ̀. 9 Awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá: o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, o si tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ: 10 Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 11 Ati ẹran ati awọ li o fi iná sun lẹhin ibudó. 12 O si pa ẹbọ sisun: awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. 13 Nwọn si mú ẹbọ sisun tọ̀ ọ wá, ti on ti ipín rẹ̀, ati ori: o si sun wọn lori pẹpẹ. 14 O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ. 15 O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju. 16 O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na. 17 O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀. 18 O si pa akọmalu ati àgbo fun ẹbọ alafia, ti iṣe ti awọn enia; awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. 19 Ati ọrá inu akọmalu na ati ti inu àgbo na, ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati eyiti o bò ifun, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ: 20 Nwọn si fi ọrá na lé ori igẹ̀ wọnni, o si sun ọrà na lori pẹpẹ. 21 Ati igẹ̀ na ati itan ọtún ni Aaroni fì li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; bi Mose ti fi aṣẹ lelẹ. 22 Aaroni si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke si awọn enia, o si sure fun wọn; o si sọkalẹ kuro ni ibi irubọ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. 23 Mose ati Aaroni si wọ̀ inu agọ́ ajọ, nwọn si jade, nwọn si sure fun awọn enia: ogo OLUWA si farahàn fun gbogbo enia. 24 Iná kan si ti ọdọ OLUWA jade wá, o si jó ẹbọ sisun ati ọrá ori pẹpẹ na; nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn hó kùhu, nwọn si dojubolẹ.

Lefitiku 10

Ẹ̀ṣẹ̀ Nadabu ati Abihu

1 ATI Nadabu ati Abihu, awọn ọmọ Aaroni, olukuluku nwọn mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari sori wọn, nwọn si mú ajeji iná wá siwaju OLUWA, ti on kò fi aṣẹ fun wọn. 2 Iná si ti ọdọ OLUWA jade, o si run wọn, nwọn si kú niwaju OLUWA. 3 Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ. 4 Mose si pé Miṣaeli ati Elsafani, awọn ọmọ Usieli arakunrin Aaroni, o si wi fun wọn pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ gbé awọn arakunrin nyin kuro niwaju ibi mimọ́ jade sẹhin ibudó. 5 Bẹ̃ni nwọn sunmọ ibẹ̀, nwọn si gbé ti awọn ti ẹ̀wu wọn jade sẹhin ibudó; bi Mose ti wi. 6 Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ máṣe ṣi ibori nyin, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fà aṣọ nyin ya; ki ẹnyin ki o má ba kú, ati ki ibinu ki o má ba wá sori gbogbo ijọ: ṣugbọn ki awọn arakunrin nyin, gbogbo ile Israeli ki o sọkun ijóna ti OLUWA ṣe yi. 7 Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.

Òfin fún Àwọn Àlùfáàa

8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, 9 Máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, iwọ, tabi awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nigbati ẹnyin ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: ìlana ni titilai ni iraniran nyin: 10 Ki ẹnyin ki o le ma fi ìyatọ sãrin mimọ́ ati aimọ́, ati sãrin ẽri ati ailẽri; 11 Ati ki ẹnyin ki o le ma kọ́ awọn ọmọ Israeli ni gbogbo ìlana ti OLUWA ti sọ fun wọn lati ọwọ́ Mose wá. 12 Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ ti o kù pe, Ẹ mú ẹbọ ohunjijẹ ti o kù ninu ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe, ki ẹ si jẹ ẹ lainí iwukàra lẹba pẹpẹ: nitoripe mimọ́ julọ ni: 13 Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi. 14 Ati igẹ̀ fifì, ati itan agbesọsoke ni ki ẹnyin ki o jẹ ni ibi mimọ́ kan; iwọ, ati awọn ọmọkunrin rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ pẹlu rẹ: nitoripe ipín tirẹ ni, ati ipín awọn ọmọ rẹ, ti a fi fun nyin ninu ẹbọ alafia awọn ọmọ Israeli. 15 Itan agbesọsoke ati igẹ̀ fifì ni ki nwọn ki o ma múwa pẹlu ẹbọ ti a fi iná ṣe ti ọrá, lati fì i fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA: yio si ma jẹ́ tirẹ, ati ti awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nipa ìlana titilai; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. 16 Mose si fi pẹlẹpẹlẹ wá ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, si kiyesi i, a ti sun u: o si binu si Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni ti o kù, wipe, 17 Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA? 18 Kiyesi i, a kò mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu ibi mimọ́: ẹnyin iba ti jẹ ẹ nitõtọ ni ibi mimọ́, bi mo ti paṣẹ. 19 Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA? 20 Nigbati Mose gbọ́ eyi inu rẹ̀ si tutù.

Lefitiku 11

Àwọn Ẹranko Tí Ó Tọ̀nà láti Jẹ

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni, o wi fun wọn pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ ninu gbogbo ẹran ti mbẹ lori ilẹ aiye. 3 Ohunkohun ti o ba yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là li ẹsẹ̀, ti o si njẹ apọjẹ, ninu ẹran, on ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 4 Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹ máṣe jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi awọn ti o si yà bàta-ẹsẹ̀: bi ibakasiẹ, nitoriti o njẹ apọjẹ ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 5 Ati gara, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 6 Ati ehoro, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 7 Ati ẹlẹdẹ̀, bi o ti yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là ẹsẹ̀, ṣugbọn on kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin. 8 Ninu ẹran wọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ, okú wọn li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn; alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin. 9 Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti mbẹ ninu omi: ohunkohun ti o ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, ninu okun, ati ninu odò, awọn ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 10 Ati gbogbo eyiti kò ní lẹbẹ ati ipẹ́ li okun, ati li odò, ninu gbogbo ohun ti nrá ninu omi, ati ninu ohun alãye kan ti mbẹ ninu omi, irira ni nwọn o jasi fun nyin, 11 Ani irira ni nwọn o ma jẹ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, okú wọn ni ẹ o sì kàsi irira. 12 Ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun. 13 Wọnyi li ẹnyin o si ma kàsi irira ninu ẹiyẹ; awọn li a kò gbọdọ jẹ, irira ni nwọn iṣe: idì, ati aṣá-idì, ati idì-ẹja. 14 Ati igún, ati aṣá li onirũru rẹ̀; 15 Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀; 16 Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀, 17 Ati òyo ati ìgo, ati owiwi; 18 Ati ogbugbu, ati ofù, ati àkala; 19 Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán. 20 Gbogbo ohun ti nrakò, ti nfò ti o si nfi mẹrẹrin rìn ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin. 21 Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti nfò, ti nrakò, ti nfi gbogbo mẹrẹrin rìn, ti o ní tete lori ẹsẹ̀ wọn, lati ma fi ta lori ilẹ; 22 Ani ninu wọnyi ni ki ẹnyin ma jẹ; eṣú ni irú rẹ̀, ati eṣú onihoho nipa irú rẹ̀, ati ọbọnbọn nipa irú rẹ̀, ati ẹlẹnga nipa irú rẹ̀. 23 Ṣugbọn gbogbo ohun iyokù ti nfò ti nrakò, ti o ní ẹsẹ̀ mẹrin, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin. 24 Nitori wọnyi li ẹnyin o si jẹ́ alaimọ́: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: 25 Ẹnikẹni ti o ba si rù ohun kan ninu okú wọn ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 26 Ẹranko gbogbo ti o yà bàta-ẹsẹ̀, ti kò si là ẹsẹ̀, tabi ti kò si jẹ apọjẹ, ki o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: gbogbo ẹniti o ba farakàn wọn ki o jẹ́ alaimọ́. 27 Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 28 Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin. 29 Wọnyi ni yio si jasi alaimọ́ fun nyin ninu ohun ti nrakò lori ilẹ; ase, ati eku, ati awun nipa irú rẹ̀. 30 Ati ọmọ̃le, ati ahanhan, ati alãmu, ati agiliti, ati agẹmọ. 31 Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 32 Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́. 33 Ati gbogbo ohunèlo amọ̀, ninu eyiti ọkan ninu okú nwọn ba bọ́ si, ohunkohun ti o wù ki o wà ninu rẹ̀ yio di alaimọ́, ki ẹnyin ki o si fọ́ ọ. 34 Ninu onjẹ gbogbo ti a o ba jẹ, ti irú omi nì ba dà si, yio di alaimọ́: ati ohun mimu gbogbo ti a o ba mu ninu irú ohunèlo na yio di alaimọ́. 35 Ati ohunkohun lara eyiti ninu okú wọn ba ṣubulù, yio di alaimọ́; iba ṣe àro, tabí idana, wiwó ni ki a wó wọn lulẹ: alaimọ́ ni nwọn, nwọn o si jẹ́ alaimọ́ fun nyin. 36 Ṣugbọn orisun tabi kanga kan, ninu eyiti omi pupọ̀ gbé wà, yio jẹ́ mimọ́: ṣugbọn eyiti o ba kàn okú wọn yio jẹ́ alaimọ́. 37 Bi ninu okú wọn ba bọ́ sara irugbìn kan ti iṣe gbigbìn, yio jẹ́ mimọ́. 38 Ṣugbọn bi a ba dà omi sara irugbìn na, ti ninu okú wọn ba si bọ́ sinu rẹ̀, yio si jẹ́ alaimọ́ fun nyin. 39 Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 40 Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 41 Ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ yio jasi irira; a ki yio jẹ ẹ. 42 Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn. 43 Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri. 44 Nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin si mimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́; nitoripe mimọ́ li Emi: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi ohunkohun ti nrakò sọ ara nyin di elẽri. 45 Nitoripe Emi li OLUWA ti o mú nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: nitorina ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́, nitoripe mimọ́ li Emi. 46 Eyiyi li ofin ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ẹda gbogbo alãye ti nrá ninu omi, ati ti ẹda gbogbo ti nrakò lori ilẹ: 47 Lati fi iyatọ sãrin aimọ́ ati mimọ́, ati sãrin ohun alãye ti a ba ma jẹ, ati ohun alãye ti a ki ba jẹ.

Lefitiku 12

Ìwẹ̀nùmọ́ Àwọn Obinrin Lẹ́yìn Ìbímọ

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi obinrin kan ba lóyun, ti o si bi ọmọkunrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; gẹgẹ bi ọjọ́ ìyasọtọ fun ailera rẹ̀ ni ki o jẹ́ alaimọ́. 3 Ni ijọ́ kẹjọ ni ki a si kọ ọmọkunrin na nilà. 4 Ki obinrin na ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọjọ́ mẹtalelọgbọ̀n; ki o máṣe fọwọkàn ohun mimọ́ kan, bẹ̃ni ki o máṣe lọ sinu ibi mimọ́, titi ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ yio fi pé. 5 Ṣugbọn bi o ba bi ọmọbinrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ li ọsẹ̀ meji, bi ti inu ìyasọtọ rẹ̀: ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọgọta ọjọ́ o le mẹfa. 6 Nigbati ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ ba pé, fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, ki o mú ọdọ-agutan ọlọdún kan wá fun ẹbọ sisun, ati ẹiyẹle, tabi àdaba, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ ajọ: 7 Ẹniti yio ru u niwaju OLUWA, ti yio si ṣètutu fun u; on o si di mimọ́ kuro ninu isun ẹ̀jẹ rẹ̀. Eyi li ofin fun ẹniti o bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. 8 Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá; ọkan fun ẹbọ sisun, ati ekeji fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: alufa yio si ṣètutu fun u, on o si di mimọ́.

Lefitiku 13

Àwọn Òfin tí ó Jẹmọ́ Àrùn Ara

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Nigbati enia kan ba ní iwú, apá, tabi àmi didán kan li awọ ara rẹ̀, ti o si mbẹ li awọ ara rẹ̀ bi àrun ẹ̀tẹ; nigbana ni ki a mú u tọ̀ Aaroni alufa wá, tabi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀, alufa: 3 Alufa yio si wò àrun ti mbẹ li awọ ara rẹ̀: bi irun ti mbẹ li oju àrun na ba si di funfun, ati ti àrun na li oju rẹ̀ ba jìn jù awọ ara rẹ̀ lọ, àrun ẹ̀tẹ ni: ki alufa ki o si wò o, ki o si pè e li alaimọ́. 4 Bi àmi didán na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ati li oju rẹ̀ ti kò si jìn jù awọ lọ, ti irun rẹ̀ kò di funfun, nigbana ni ki alufa ki o sé alarun na mọ́ ni ijọ́ meje: 5 Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba duro li oju rẹ̀, ti àrun na kò ba si ràn li ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje si i: 6 Ki alufa ki o si tun wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba ṣe bi ẹni wodú, ti àrun na kò si ràn si i li awọ ara, ki alufa ki o pè e ni mimọ́: kìki apá ni: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o jẹ́ mimọ́. 7 Ṣugbọn bi apá na ba ràn pupọ̀ si i li awọ ara, lẹhin igbati alufa ti ri i tán fun mimọ́ rẹ̀, alufa yio si tun wò o. 8 Alufa yio wò o, kiyesi i, apá na ràn li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ẹ̀tẹ ni. 9 Nigbati àrun ẹ̀tẹ ba mbẹ li ara enia, nigbana ni ki a mú u tọ̀ alufa wá; 10 Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na, 11 Ẹ̀tẹ lailai ni li awọ ara rẹ̀, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ki o máṣe sé e mọ́; nitoripe alaimọ́ ni. 12 Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò; 13 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi ẹ̀tẹ na ba bò gbogbo ara rẹ̀, ki o pè àlarun na ni mimọ́; gbogbo rẹ̀ di funfun: mimọ́ li on. 14 Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́. 15 Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni. 16 Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá, 17 Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on. 18 Ara pẹlu, ninu eyi, ani li awọ ara ti õwo ti sọ, ti o si jiná, 19 Ati ni apá õwo na bi iwú funfun ba mbẹ nibẹ̀, tabi àmi didán, funfun ti o si ṣe bi ẹni pọ́n ki a si fi i hàn alufa; 20 Alufa yio wò o, si kiyesi i, li oju rẹ̀ bi o ba jìn jù awọ ara lọ, ti irun rẹ̀ si di funfun, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu õwo na. 21 Ṣugbọn bi alufa na ba wò o, si kiyesi i, ti irun funfun kò si sí ninu rẹ̀, bi kò ba si jìn jù awọ ara lọ, ti o si dabi ẹni wodú, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje: 22 Bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ni. 23 Ṣugbọn bi àmi didán na ba duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn, õwo tita ni; ki alufa ki o si pè e ni mimọ́. 24 Tabi bi ara kan ba mbẹ, ninu awọ ara eyiti ijóni bi iná ba wà, ti ojú jijóna na ba ní àmi funfun didán, ti o ṣe bi ẹni pọn rusurusu tabi funfun; 25 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi irun ninu àmi didán na ba di funfun, ti o ba si jìn jù awọ ara lọ li oju; ẹ̀tẹ li o ti inu ijóni nì sọ jade; nitorina ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ ni. 26 Ṣugbọn bi alufa ba wò o, si kiyesi i, ti kò sí irun funfun li apá didán na, ti kò si jìn jù awọ ara iyokù lọ, ṣugbọn ti o ṣe bi ẹni ṣújú; nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje: 27 Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́; àrun ẹ̀tẹ ni. 28 Bi àmi didán na ba si duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn si i li awọ ara, ṣugbọn ti o dabi ẹni sújú: iwú ijóni ni, ki alufa ki o si pè e ni mimọ́: nitoripe ijóni tita ni. 29 Bi ọkunrin tabi obinrin kan ba ní àrun li ori rẹ̀ tabi li àgbọn, 30 Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni. 31 Bi alufa ba si wò àrun pipa na, si kiyesi i, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju, ti kò si sí irun dudu ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé àlarun pipa na mọ́ ni ijọ́ meje: 32 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò àrun na: si kiyesi i, bi pipa na kò ba ràn, ti kò si sí irun pupa ninu rẹ̀, ti pipa na kò si jìn jù awọ ara lọ li oju, 33 Ki o fári, ṣugbọn ki o máṣe fá ibi pipa na; ki alufa ki o si sé ẹni pipa nì mọ́ ni ijọ́ meje si i: 34 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́. 35 Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀; 36 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni. 37 Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́. 38 Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán; 39 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on. 40 Ati ọkunrin ti irun rẹ̀ ba re kuro li ori rẹ̀, apari ni; ṣugbọn mimọ́ li on. 41 Ẹniti irun rẹ̀ ba re silẹ ni ìha iwaju rẹ̀, o pari ni iwaju; ṣugbọn mimọ́ li on. 42 Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na. 43 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi iwú õju na ba funfun-pupa rusurusu ni pipa ori rẹ̀, tabi pipa iwaju rẹ̀, bi ẹ̀tẹ ti ihàn li awọ ara; 44 Ẹlẹtẹ ni, alaimọ́ ni: ki alufa ki o pè e li aimọ́ patapata; àrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀. 45 Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́. 46 Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Kí Nǹkan Séèébu

47 Ati aṣọ ti àrun ẹ̀tẹ mbẹ ninu rẹ̀, iba ṣe aṣọ kubusu, tabi aṣọ ọ̀gbọ; 48 Iba ṣe ni ita, tabi ni iwun; ti ọ̀gbọ, tabi ti kubusu; iba ṣe li awọ, tabi ohun kan ti a fi awọ ṣe; 49 Bi àrun na ba ṣe bi ọbẹdo tabi bi pupa lara aṣọ na, tabi lara awọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo awọ kan; àrun ẹ̀tẹ ni, ki a si fi i hàn alufa: 50 Ki alufa ki o si wò àrun na, ki o si sé ohun ti o ní àrun na mọ́ ni ijọ́ meje: 51 Ki o si wò àrun na ni ijọ́ keje: bi àrun na ba ràn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu awọ, tabi ninu ohun ti a fi awọ ṣe; àrun oun ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; alaimọ́ ni. 52 Nitorina ki o fi aṣọ na jóna, iba ṣe ita, tabi iwun, ni kubusu tabi li ọ̀gbọ, tabi ninu ohunèlo awọ kan, ninu eyiti àrun na gbé wà: nitoripe ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; ki a fi jóna. 53 Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na kò ba tàn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe; 54 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o fọ̀ ohun na ninu eyiti àrun na gbé wà, ki o si sé e mọ́ ni ijọ meje si i. 55 Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode. 56 Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na ba ṣe bi ẹni wodú lẹhin igbati o ba fọ̀ ọ tán; nigbana ni ki o fà a ya kuro ninu aṣọ na, tabi ninu awọ na, tabi ninu ita, tabi ninu iwun: 57 Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀. 58 Ati aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunkohun ti a fi awọ ṣe, ti iwọ ba fọ̀, bi àrun na ba wọ́n kuro ninu wọn nigbana ni ki a tun fọ̀ ọ lẹkeji, on o si jẹ́ mimọ́. 59 Eyi li ofin àrun ẹ̀tẹ, ninu aṣọ, kubusu tabi ti ọ̀gbọ, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ohunkohun èlo awọ kan, lati pè e ni mimọ́, tabi lati pè e li aimọ́.

Lefitiku 14

Ìwẹ̀nùmọ́ lẹ́yìn Àrùn Ara

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Eyi ni yio ma ṣe ofin adẹ́tẹ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀: ki a mú u tọ̀ alufa wá: 3 Ki alufa ki o si jade sẹhin ibudó; ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi àrun ẹ̀tẹ na ba jiná li ara adẹ́tẹ na: 4 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ pe, ki a mú ãye ẹiyẹ meji mimọ́ wá, fun ẹniti a o wẹ̀numọ́, pẹlu igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu: 5 Ki alufa ki o paṣẹ pe ki a pa ọkan ninu ẹiyẹ nì ninu ohunèlo àmọ li oju omi ti nṣàn: 6 Niti ẹiyẹ alãye, ki o mú u, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu, ki o si fi wọn ati ẹiyẹ alãye nì bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa li oju omi ti nṣàn: 7 Ki o si fi wọ́n ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu ẹ̀tẹ nigba meje, ki o si pè e ni mimọ́, ki o si jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ si gbangba oko. 8 Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje. 9 Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́. 10 Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan. 11 Ki alufa ti o sọ ọ di mimọ́ ki o mú ọkunrin na ti a o sọ di mimọ́, ati nkan wọnni wá, siwaju OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: 12 Ki alufa ki o mú akọ ọdọ-agutan kan, ki o si fi i ru ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: 13 Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni: 14 Ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki alufa ki o si fi i si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀: 15 Ki alufa ki o si mú ninu oróro òṣuwọn logu na, ki o si dà a si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀: 16 Ki alufa ki o si tẹ̀ ika rẹ̀ ọtún bọ̀ inu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀, ki o si fi ika rẹ̀ ta ninu oróro na nigba meje niwaju OLUWA: 17 Ati ninu oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ ni ki alufa ki o fi si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, lori ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: 18 Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o dà si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́: ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA. 19 Ki alufa ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu aimọ́ rẹ̀; lẹhin eyinì ni ki o pa ẹran ẹbọ sisun. 20 Ki alufa ki o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori pẹpẹ: ki alufa ki o ṣètutu fun u, on o si di mimọ́. 21 Bi o ba si ṣe talaka, ti kò le mú tobẹ̃ wá, njẹ ki o mú akọ ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹbi lati fì, lati ṣètutu fun u, ati ọkan ninu idamẹwa òṣuwọn deali iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ, ati òṣuwọn logu oróro kan; 22 Ati àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji, irú eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to; ki ọkan ki o si ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki ekeji ki o si ṣe ẹbọ sisun. 23 Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá ni ijọ́ kẹjọ fun ìwẹnumọ́ rẹ̀, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, niwaju OLUWA. 24 Ki alufa ki o si mú ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 25 Ki o si pa ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki o si fi i si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀. 26 Ki alufa ki o si dà ninu oróro na si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀: 27 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ ọtún ta ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀ nigba meje niwaju OLUWA: 28 Ki alufa ki o si fi ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, si ibi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi: 29 Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o fi si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́, lati ṣètutu fun u niwaju OLUWA. 30 Ki o si fi ọkan ninu àdaba nì rubọ, tabi ọkan ninu ọmọ ẹiyẹle nì, iru eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to: 31 Ani irú eyiti apa rẹ̀ ka, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ niwaju OLUWA. 32 Eyi li ofin rẹ̀ li ara ẹniti àrun ẹ̀tẹ wà, apa ẹniti kò le ka ohun ìwẹnumọ́ rẹ̀.

Bí Ara Ògiri Bá Séèébu

33 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 34 Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, ti mo fi fun nyin ni ilẹ-iní, ti mo ba si fi àrun ẹ̀tẹ sinu ile kan ninu ilẹ-iní nyin; 35 Ti onile na si wá ti o si wi fun alufa pe, O jọ li oju mi bi ẹnipe àrun mbẹ ninu ile na: 36 Nigbana ni ki alufa ki o fun wọn li aṣẹ, ki nwọn ki o kó ohun ile na jade, ki alufa ki o to wọ̀ inu rẹ̀ lọ lati wò àrun na, ki ohun gbogbo ti mbẹ ninu ile na ki o máṣe jẹ́ alaimọ́: lẹhin eyinì ni ki alufa ki o wọ̀ ọ lati wò ile na: 37 Ki o si wò àrun na, si kiyesi i, bi àrun na ba mbẹ lara ogiri ile na pẹlu ìla gbòrogbòro, bi ẹni ṣe bi ọbẹdò tabi pupa rusurusu, ti o jìn li oju jù ogiri lọ; 38 Nigbana ni ki alufa ki o jade ninu ile na si ẹnu-ọ̀na ile na, ki o si há ilẹkun ile na ni ijọ́ meje: 39 Ki alufa ki o tun wá ni ijọ́ keje, ki o si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba ràn lara ogiri ile na; 40 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o yọ okuta na kuro lara eyiti àrun na gbé wà, ki nwọn ki o si kó wọn lọ si ibi aimọ́ kan lẹhin ilu na: 41 Ki o si mu ki nwọn ki o ha inu ile na yiká kiri, ki nwọn ki o kó erupẹ ti a ha nì kuro lọ si ẹhin ilu na si ibi aimọ́ kan: 42 Ki nwọn ki o si mú okuta miran, ki nwọn ki o si fi i di ipò okuta wọnni, ki nwọn ki o si mú ọrọ miran ki nwọn ki o si fi rẹ́ ile na. 43 Bi àrùn na ba si tun pada wá, ti o si tun sọ jade ninu ile na, lẹhin igbati nwọn ba yọ okuta wọnni kuro, ati lẹhin igbati nwọn ba ha ile na, ati lẹhin igbati nwọn ba rẹ́ ẹ; 44 Nigbana ni ki alufa ki o wá, ki o wò o, si kiyesi i, bi àrun ba ràn si i ninu ile na, ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni mbẹ ninu ile na: aimọ́ ni. 45 Ki o si wó ile na, okuta rẹ̀, ati ìti igi rẹ̀, ati gbogbo erupẹ ile na; ki o si kó wọn jade kuro ninu ilu na lọ si ibi aimọ́ kan. 46 Ẹniti o ba si wọ̀ ile na ni gbogbo ìgba na ti a sé e mọ́, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 47 Ẹniti o ba dubulẹ ninu ile na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀: ẹniti o jẹun ninu ile na ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀. 48 Ati bi alufa ba wọ̀ ile, ti o si wò o, si kiyesi i, ti àrun inu ile na kò ba ràn si i, lẹhin igbati a rẹ́ ile na tán; nigbana ni ki alufa ki o pè ile na ni mimọ́, nitoripe àrun na ti jiná. 49 Ki o si mú ẹiyẹ meji, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu wá, lati wẹ̀ ile na mọ́: 50 Ki o si pa ọkan ninu ẹiyẹ na, ninu ohunèlo amọ loju omi ti nṣàn: 51 Ki o si mú igi opepe, ati ewe-hissopu, ati ododó, ati ẹiyẹ alãye nì, ki o si tẹ̀ wọn bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa nì, ati ninu omi ṣiṣàn nì, ki o si fi wọ́n ile na nigba meje: 52 Ki o si fi ẹ̀jẹ ẹiyẹ na wẹ̀ ile na mọ́, ati pẹlu omi ṣiṣàn nì, ati pẹlu ẹiyẹ alãye nì, ati pẹlu igi opepe nì, ati pẹlu ewe-hissopu nì, ati pẹlu ododó: 53 Ṣugbọn ki o jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ kuro ninu ilu lọ sinu gbangba oko, ki o si ṣètutu si ile na: yio si di mimọ́. 54 Eyi li ofin fun gbogbo onirũru àrun ẹ̀tẹ, ati ipẹ́; 55 Ati fun ẹ̀tẹ aṣọ, ati ti ile; 56 Ati fun wiwu, ati fun apá, ati fun àmi didán: 57 Lati kọni nigbati o ṣe alaimọ́, ati nigbati o ṣe mimọ́: eyi li ofin ẹ̀tẹ.

Lefitiku 15

Àwọn Ohun Àìmọ́ tí Ń Jáde Lára

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on. 3 Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe. 4 Gbogbo ori akete ti ẹniti o ní isun na ba dubulẹ lé, aimọ́ ni: ati gbogbo ohun ti o joko lé yio jẹ́ alaimọ́. 5 Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 6 Ẹniti o si joko lé ohunkohun ti ẹniti o ní isun ti joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 7 Ẹniti o si farakàn ara ẹniti o ní isun, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 8 Bi ẹniti o ní isun ba tutọ sara ẹniti o mọ́; nigbana ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 9 Ati asákasá ti o wù ki ẹniti o ní isun ki o gùn ki o jẹ́ alaimọ́. 10 Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 11 Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 12 Ati ohunèlo amọ̀, ti ẹniti o ní isun ba fọwọkàn, fifọ́ ni ki a fọ́ ọ: ati gbogbo ohunèlo igi ni ki a ṣàn ninu omi. 13 Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́. 14 Ati ni ijọ́ kẹjọ, ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si fi wọn fun alufa: 15 Ki alufa ki o si fi wọn rubọ, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun rẹ̀. 16 Ati bi ohun irú ìdapọ ọkunrin ba ti ara rẹ̀ jade, nigbana ni ki o wẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 17 Ati gbogbo aṣọ, ati gbogbo awọ, lara eyiti ohun irú ìdapọ ba wà, on ni ki a fi omi fọ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 18 Ati obinrin na, ẹniti ọkunrin ba bá dàpọ ti on ti ohun irú ìdapọ, ki awọn mejeji ki o wẹ̀ ninu omi, ki nwọn ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 19 Bi obinrin kan ba si ní isun, ti isun rẹ̀ li ara rẹ̀ ba jasi ẹ̀jẹ, ki a yà a sapakan ni ijọ́ meje: ẹnikẹni ti o ba si farakàn a, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 20 Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́. 21 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 22 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 23 Bi o ba si ṣepe lara akete rẹ̀ ni, tabi lara ohun ti o joko lé, nigbati o ba farakàn a, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 24 Bi ọkunrin kan ba si bá a dàpọ rára, ti ohun obinrin rẹ̀ ba mbẹ lara ọkunrin na, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; ati gbogbo akete ti on dubulẹ lé ki o jẹ́ aimọ́. 25 Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́. 26 Gbogbo akete ti o dubulẹ lé ni gbogbo ọjọ́ isun rẹ̀ ki o si jẹ́ fun u bi akete ìyasapakan rẹ̀: ati ohunkohun ti o joko lé ki o jẹ́ aimọ́, bi aimọ́ ìyasapakan rẹ̀. 27 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn nkan wọnni ki o jẹ́ alaimọ́, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ̀ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 28 Ṣugbọn bi obinrin na ba di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, lẹhin eyinì ni ki o si jẹ́ mimọ́. 29 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 30 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun aimọ́ rẹ̀. 31 Bayi ni ki ẹnyin ki o yà awọn ọmọ Israeli kuro ninu aimọ́ wọn; ki nwọn ki o má ba kú ninu aimọ́ wọn, nigbati nwọn ba sọ ibugbé mi ti mbẹ lãrin wọn di aimọ́. 32 Eyi li ofin ẹniti o ní isun, ati ti ẹniti ohun irú rẹ̀ jade lara rẹ̀, ti o si ti ipa rẹ̀ di alaimọ́; 33 Ati ti ẹniti o ri ohun obinrin rẹ̀, ati ti ẹniti o ní isun, ati ti ọkunrin, ati ti obinrin, ati ti ẹniti o ba bá ẹniti iṣe alaimọ́ dàpọ.

Lefitiku 16

Ọjọ́ Ètùtù

1 OLUWA si sọ fun Mose lẹhin ikú awọn ọmọ Aaroni meji, nigbati nwọn rubọ niwaju OLUWA, ti nwọn si kú; 2 OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu. 3 Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun. 4 Ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ mimọ́ wọ̀, ki o si bọ̀ ṣòkoto ọ̀gbọ nì si ara rẹ̀, ki a si fi amure ọ̀gbọ kan dì i, fila ọ̀gbọ ni ki a fi ṣe e li ọṣọ́: aṣọ mimọ́ ni wọnyi; nitorina ni o ṣe wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si mú wọn wọ̀. 5 Ki o si gbà ọmọ ewurẹ meji akọ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan fun ẹbọ sisun, lọwọ ijọ awọn ọmọ Israeli. 6 Ki Aaroni ki o si fi akọmalu ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikara rẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀. 7 Ki o si mú ewurẹ meji nì, ki o si mú wọn wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 8 Ki Aaroni ki o si di ìbo ewurẹ meji na; ìbo kan fun OLUWA, ati ìbo keji fun Asaseli (ewurẹ idasilẹlọ). 9 Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 10 Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli. 11 Ki Aaroni ki o si mú akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá, ti iṣe ti on tikararẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ki o si pa akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti iṣe fun ara rẹ̀: 12 Ki o si mú awo-turari ti o kún fun ẹyin iná lati ori pẹpẹ wá lati iwaju OLUWA, ki ọwọ́ rẹ̀ ki o si kún fun turari didùn ti a gún kunná, ki o si mú u wá sinu aṣọ-ikele: 13 Ki o si fi turari na sinu iná niwaju OLUWA, ki ẽfin turari ki o le bò itẹ́-ãnu ti mbẹ lori ẹri, ki on ki o má ba kú. 14 Ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si fi ika rẹ̀ wọn ọ sori itẹ́-ãnu ni ìha ìla-õrùn; ati niwaju itẹ́-ãnu ni ki o fi ìka rẹ̀ wọ́n ninu ẹ̀jẹ na nigba meje. 15 Nigbana ni ki o pa ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, eyiti iṣe ti awọn enia, ki o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu aṣọ-ikele, ki o si fi ẹ̀jẹ na ṣe bi o ti fi ẹ̀jẹ akọmalu ṣe, ki o si fi wọ́n ori itẹ̀-ãnu, ati niwaju itẹ́-ãnu: 16 Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́ nì, nitori aimọ́ awọn ọmọ Israeli, ati nitori irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn: bẹ̃ni ki o si ṣe si agọ́ ajọ, ti mbẹ lọdọ wọn ninu aimọ́ wọn. 17 Ki o má si sí ẹnikan ninu agọ́ ajọ nigbati o ba wọle lati ṣètutu ninu ibi mimọ́, titi yio fi jade, ti o si ti ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ati fun gbogbo ijọ enia Israeli. 18 Ki o si jade si ibi pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ki o si ṣètutu si i; ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ati ninu ẹ̀jẹ ewurẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ na yiká. 19 Ki o si fi ika rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na wọ́n ara rẹ̀ nigba meje, ki o si wẹ̀ ẹ mọ́, ki o si yà a simimọ́ kuro ninu aimọ́ awọn ọmọ Israeli.

Ewúrẹ́ tí A Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ lé Lórí

20 Nigbati o ba si pari ati ṣètutu si ibi mimọ́, ati si agọ́ ajọ, ati pẹpẹ, ki o mú ewurẹ alãye nì wá: 21 Ki Aaroni ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ mejeji lé ori ewurẹ alãye na, ki o si jẹwọ gbogbo aiṣedede awọn ọmọ Israeli sori rẹ̀, ati gbogbo irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn; ki o si fi wọn lé ori ewurẹ na, ki o si ti ọwọ́ ẹniti o yẹ rán a lọ si ijù: 22 Ki ewurẹ na ki o si rù gbogbo aiṣedede wọn lori rẹ̀ lọ si ilẹ ti a kò tẹ̀dó: ki o si jọwọ ewurẹ na lọwọ lọ sinu ijù. 23 Ki Aaroni ki o si wá sinu agọ́ ajọ, ki o si bọ́ aṣọ ọ̀gbọ wọnni silẹ, ti o múwọ̀ nigbati o wọ̀ ibi mimọ́ lọ, ki o si fi wọn sibẹ̀: 24 Ki o si fi omi wẹ̀ ara rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan, ki o si mú aṣọ rẹ̀ wọ̀, ki o si jade wá, ki o si ru ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ sisun awọn enia, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀ ati fun awọn enia. 25 Ọrá ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì ni ki o si sun lori pẹpẹ. 26 Ati ẹniti o jọwọ ewurẹ nì lọwọ lọ fun Asaseli, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó. 27 Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná. 28 Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.

Ìlànà fún Ìrántí Ọjọ́ Ètùtù

29 Eyi ni ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin: pe li oṣù keje, li ọjọ́ kẹwa oṣù, ni ki ẹnyin ki o pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹnyin má si ṣe iṣẹ kan rára, iba ṣe ibilẹ, tabi alejò ti nṣe atipo lãrin nyin: 30 Nitoripe li ọjọ́ na li a o ṣètutu fun nyin, lati wẹ̀ nyin mọ́; ki ẹnyin ki o le mọ́ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin niwaju OLUWA. 31 On o jẹ́ ọjọ́ isimi fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, nipa ìlana titilai. 32 Ati alufa na, ẹniti a o ta oróro si li ori, ati ẹniti a o yàsimimọ́ si iṣẹ-alufa dipò baba rẹ̀, on ni ki o ṣètutu na, ki o si mú aṣọ ọ̀gbọ wọnni wọ̀, ani aṣọ mimọ́ wọnni: 33 Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́, ki o si ṣètutu si agọ́ ajọ, ati si pẹpẹ; ki o si ṣètutu fun awọn alufa, ati fun gbogbo ijọ enia. 34 Ki eyi ki o si jẹ́ ìlana titilai fun nyin, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli nitori ẹ̀ṣẹ wọn gbogbo lẹ̃kan li ọdún. O si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Lefitiku 17

Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ̀–Ninu Rẹ̀ Ni Ẹ̀mí wà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe; Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, wipe, 3 Ẹnikẹni ti iṣe enia ile Israeli, ti o ba pa akọmalu tabi ọdọ-agutan, tabi ewurẹ, ninu ibudó, tabi ti o pa a lẹhin ibudó, 4 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u li ẹbọ wi OLUWA niwaju agọ́ OLUWA: a o kà ẹ̀jẹ si ọkunrin na lọrùn, o ta ẹ̀jẹ silẹ; ọkunrin na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: 5 Nitori idí eyi pe, ki awọn ọmọ Israeli ki o le ma mú ẹbọ wọn wá, ti nwọn ru ni oko gbangba, ani ki nwọn ki o le mú u tọ̀ OLUWA wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, sọdọ alufa, ki o si ru wọn li ẹbọ alafia si OLUWA. 6 Ki alufa ki o si bù ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si sun ọrá na fun õrùn didún si OLUWA. 7 Ki nwọn ki o má si ṣe ru ẹbọ wọn si obukọ mọ́, ti nwọn ti ntọ̀ lẹhin ṣe àgbere. Eyi ni yio ma ṣe ìlana lailai fun wọn ni iran-iran wọn. 8 Ki iwọ ki o si wi fun wọn, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ru ẹbọ sisun tabi ẹbọ kan, 9 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u si OLUWA; ani ọkunrin na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 10 Ati ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ; ani emi o kọ oju mi si ọkàn na ti o jẹ ẹ̀jẹ, emi o si ke e kuro ninu awọn enia rẹ̀. 11 Nitoripe ẹmi ara mbẹ ninu ẹ̀jẹ: emi si ti fi i fun nyin lati ma fi ṣètutu fun ọkàn nyin lori pẹpẹ nì: nitoripe ẹ̀jẹ ni iṣe ètutu fun ọkàn. 12 Nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọkàn kan ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ, bẹ̃li alejò kan ti nṣe atipo ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ. 13 Ati ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti nṣe ọdẹ ti o si mú ẹranko tabi ẹiyẹ ti a ba jẹ; ani ki o ro ẹ̀jẹ rẹ̀ dànu, ki o si fi erupẹ bò o. 14 Nitoripe ẹmi gbogbo ara ni, ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ẹmi rẹ̀: nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ ẹrankẹran: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi ara gbogbo: ẹnikẹni ti o ba jẹ ẹ li a o ke kuro. 15 Ati gbogbo ọkàn ti o ba jẹ ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, tabi eyiti a fàya, iba ṣe ọkan ninu awọn ibilẹ, tabi alejò, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: nigbana li on o mọ́. 16 Ṣugbọn bi kò ba fọ̀ wọn, tabi ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀; njẹ on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

Lefitiku 18

Àwọn Èèwọ̀ tí Ó Jẹmọ́ Bíbá Obinrin Lòpọ̀

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 3 Ẹnyin kò gbọdọ hùwa bi ìwa ilẹ Egipti nibiti ẹnyin ti ngbé: ẹnyin kò si gbọdọ hùwa ìwa ilẹ Kenaani, nibiti emi o mú nyin lọ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ rìn nipa ìlana wọn. 4 Ki ẹnyin ki o ma ṣe ofin mi, ki ẹnyin si ma pa ìlana mi mọ́, lati ma rìn ninu wọn: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 5 Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA. 6 Ẹnikẹni kò gbọdọ sunmọ ẹnikan ti iṣe ibatan rẹ̀ lati tú ìhoho rẹ̀: Emi li OLUWA. 7 Ihoho baba rẹ, tabi ìhoho iya rẹ̀, ni iwọ kò gbọdọ tú: iya rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀. 8 Ihoho aya baba rẹ ni iwọ kò gbọdọ tú: ìhoho baba rẹ ni. 9 Ihoho arabinrin rẹ, ọmọ baba rẹ, tabi ọmọ iya rẹ, ti a bi ni ile, tabi ti a bi li ode, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú. 10 Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn. 11 Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀. 12 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni. 13 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni. 14 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni. 15 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀. 16 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni. 17 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni. 18 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye. 19 Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀. 20 Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀. 21 Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. 22 Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni. 23 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni. 24 Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́: 25 Ilẹ na si dibajẹ́: nitorina ni mo ṣe bẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wò lori rẹ̀, ilẹ tikararẹ̀ si bì awọn olugbé rẹ̀ jade. 26 Nitorina ni ki ẹnyin ki o ṣe ma pa ìlana ati ofin mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọkan ninu irira wọnyi; tabi ẹnikan ninu ibilẹ nyin, tabi alejò ti nṣe atipo ninu nyin: 27 Nitoripe gbogbo irira wọnyi li awọn ọkunrin ilẹ na ṣe, ti o ti wà ṣaju nyin, ilẹ na si dibajẹ́; 28 Ki ilẹ na ki o má ba bì nyin jade pẹlu, nigbati ẹnyin ba bà a jẹ́, bi o ti bì awọn orilẹ-ède jade, ti o ti wà ṣaju nyin. 29 Nitoripe ẹnikẹni ti o ba ṣe ọkan ninu irira wọnyi, ani ọkàn wọnni ti o ba ṣe wọn li a o ke kuro lãrin awọn enia wọn. 30 Nitorina ni ki ẹnyin ki o pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ọkan ninu irira wọnyi, ti nwọn ti ṣe ṣaju nyin, ki ẹnyin ki o má si bà ara nyin jẹ́ ninu rẹ̀: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Lefitiku 19

Àwọn Òfin Tí Wọ́n Jẹmọ́ Ẹ̀tọ́ ati Jíjẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi OLUWA Ọlọrun nyin jẹ́ mimọ́. 3 Ki olukuluku nyin ki o bẹ̀ru iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 4 Ẹ máṣe yipada si ere, bẹ̃ni ki ẹnyin má si ṣe ṣe oriṣa didà fun ara nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 5 Bi ẹnyin ba si ru ẹbọ alafia si OLUWA, ki ẹnyin ki o ru u ki ẹ le di ẹni itẹwọgbà. 6 Li ọjọ́ ti ẹnyin ru ẹbọ na ni ki a jẹ ẹ, ati ni ijọ́ keji: bi ohun kan ba si kù ninu rẹ̀ titi di ijọ́ kẹta, ninu iná ni ki a sun u. 7 Bi a ba si jẹ ninu rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, irira ni; ki yio dà: 8 Nitorina ẹniti o ba jẹ ẹ ni yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀, nitoriti o bà ohun mimọ́ OLUWA jẹ́: ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 9 Ati nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa igun oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pa èṣẹ́ ikore rẹ. 10 Iwọ kò si gbọdọ pèṣẹ́ ọgbà-àjara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká gbogbo àjara ọgbà-àjara rẹ; ki iwọ ki o fi wọn silẹ fun awọn talaka ati alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 11 Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin. 12 Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. 13 Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀. 14 Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. 15 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ. 16 Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA. 17 Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18 Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA. 19 Ki ẹnyin ki o pa ìlana mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ẹranọ̀sin rẹ ki o ba onirũru dàpọ: iwọ kò gbọdọ fọ́n daru-dàpọ irugbìn si oko rẹ: bẹ̃li aṣọ ti a fi ọ̀gbọ ati kubusu hun pọ̀ kò gbọdọ kan ara rẹ. 20 Ati ẹnikẹni ti o ba bá obinrin dàpọ, ti iṣe ẹrú, ti a fẹ́ fun ọkọ, ti a kò ti ràpada rára, ti a kò ti sọ di omnira; ọ̀ran ìna ni; ki a máṣe pa wọn, nitoriti obinrin na ki iṣe omnira. 21 Ki ọkunrin na ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ani àgbo kan fun ẹbọ ẹbi. 22 Ki alufa ki o si fi àgbo ẹbọ ẹbi ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da: a o si dari ẹ̀ṣẹ ti o da jì i. 23 Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ. 24 Ṣugbọn li ọdún kẹrin, gbogbo eso rẹ̀ na ni yio jẹ́ mimọ́, si ìyin OLUWA. 25 Ati li ọdún karun ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu eso rẹ̀, ki o le ma mú ibisi rẹ̀ wá fun nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 26 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohun kan ti on ti ẹ̀jẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe ifaiya, tabi ṣe akiyesi ìgba. 27 Ẹnyin kò gbọdọ gẹ̀ ori nyin, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tọ́ irungbọn rẹ. 28 Ẹnyin kò gbọdọ sín gbẹ́rẹ kan si ara nyin nitori okú, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ kọ àmi kan si ara nyin: Emi li OLUWA. 29 Máṣe bà ọmọ rẹ obinrin jẹ́, lati mu u ṣe àgbere; ki ilẹ na ki o má ba di ilẹ àgbere, ati ki ilẹ na má ba kún fun ìwabuburu. 30 Ki ẹnyin ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́, ki ẹnyin ki o si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA. 31 Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 32 Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori-ewú, ki o si bọ̀wọ fun oju arugbo, ki o si bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. 33 Ati bi alejò kan ba nṣe atipo pẹlu rẹ ni ilẹ nyin, ẹnyin kò gbọdọ ni i lara. 34 Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 35 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu. 36 Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá. 37 Nitorina ni ki ẹnyin ki o si ma kiyesi gbogbo ìlana mi, ati si gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.

Lefitiku 20

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa. 3 Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́. 4 Bi awọn enia ilẹ na ba si mú oju wọn kuro lara ọkunrin na, nigbati o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, ti nwọn kò si pa a: 5 Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn. 6 Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀. 7 Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 8 Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́. 9 Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀. 10 Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ. 11 Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. 12 Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn. 13 Ati ọkunrin ti o ba bá ọkunrin dàpọ, bi ẹni ba obinrin dàpọ, awọn mejeji li o ṣe ohun irira: pipa li a o pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. 14 Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin. 15 Ati ọkunrin ti o ba bá ẹranko dàpọ, pipa ni ki a pa a: ki ẹnyin ki o si pa ẹranko na. 16 Bi obinrin kan ba si sunmọ ẹranko kan, lati dubulẹ tì i, ki iwọ ki o pa obinrin na, ati ẹranko na: pipa ni ki a pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn. 17 Ati bi ọkunrin kan ba fẹ́ arabinrin rẹ̀, ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀, ti o si ri ìhoho rẹ̀, ti on si ri ìhoho rẹ̀; ohun buburu ni; a o si ke wọn kuro loju awọn enia wọn: o tú ìhoho arabinrin rẹ̀; on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18 Ati bi ọkunrin kan ba bá obinrin dàpọ ti o ní ohun obinrin rẹ̀ lara, ti o ba si tú u ni ìhoho; o tú isun rẹ̀ ni ìhoho, obinrin na si fi isun ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn: awọn mejeji li a o si ke kuro lãrin awọn enia wọn. 19 Iwọ kò si gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ, tabi ti arabinrin baba rẹ: nitoripe o tú ìhoho ibatan rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn. 20 Bi ọkunrin kan ba si bá aya arakunrin õbi rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho arakunrin õbi rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn; nwọn o kú li ailọmọ. 21 Bi ọkunrin kan ba si fẹ́ aya arakunrin rẹ̀, ohun-aimọ́ ni: o tú ìhoho arakunrin rẹ̀; nwọn o jẹ́ alailọmọ. 22 Nitorina li ẹnyin o ṣe ma pa gbogbo ìlana mi mọ́, ati gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: ki ilẹ na, ninu eyiti mo mú nyin wá tẹ̀dó si, ki o má ṣe bì nyin jade. 23 Ẹnyin kò si gbọdọ rìn ninu ìlana orilẹ-ède, ti emi lé jade kuro niwaju nyin: nitoriti nwọn ṣe gbogbo wọnyi, nitorina ni mo ṣe korira wọn. 24 Ṣugbọn emi ti wi fun nyin pe, Ẹnyin o ní ilẹ wọn, ati pe emi o fi i fun nyin lati ní i, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède. 25 Nitorina ki ẹnyin ki o fi ìyatọ sãrin ẹranko mimọ́ ati alaimọ́, ati sãrin ẹiyẹ alaimọ́ ati mimọ́: ki ẹnyin ki o má si ṣe fi ẹranko, tabi ẹiyẹ, tabi ohunkohun alãye kan ti nrakò lori ilẹ, ti mo ti yàsọ̀tọ fun nyin bi alaimọ́, sọ ọkàn nyin di irira. 26 Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi. 27 Ọkunrin pẹlu tabi obinrin ti o ní ìmo afọṣẹ, tabi ti iṣe ajẹ́, pipa ni ki a pa a: okuta ni ki a fi sọ wọn pa: ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.

Lefitiku 21

Àwọn Àlùfáàa Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu awọn enia rẹ̀ kò gbọdọ di alaimọ́ nitori okú. 2 Bikoṣe fun ibatan rẹ̀ ti o sunmọ ọ, eyinì ni, iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin, ati arakunrin rẹ̀; 3 Ati arabinrin rẹ̀ ti iṣe wundia, ti o wà lọdọ rẹ̀, ti kò ti ilí ọkọ, nitori rẹ̀ ni ki o di alaimọ́. 4 Ṣugbọn on kò gbọdọ ṣe ara rẹ̀ li aimọ́, lati bà ara rẹ̀ jẹ́, olori kan sa ni ninu awọn enia rẹ̀. 5 Nwọn kò gbọdọ dá ori wọn fá, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ tọ́ irungbọn wọn, tabi singbẹrẹ kan si ara wọn. 6 Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́. 7 Nwọn kò gbọdọ fẹ́ aya ti iṣe àgbere, tabi ẹni ibàjẹ́; bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fẹ́ obinrin ti a ti ọdọ ọkọ rẹ̀ kọ̀silẹ: nitoripe mimọ́ li on fun Ọlọrun rẹ̀. 8 Nitorina ki ẹnyin ki o yà a simimọ́; nitoriti o nrubọ àkara Ọlọrun rẹ: yio jẹ́ mimọ́ si ọ: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, ti o yà nyin simimọ́. 9 Ati bi ọmọbinrin alufa kan, ba fi iṣẹ àgbere bà ara rẹ̀ jẹ́, o bà baba rẹ̀ jẹ́: iná li a o da sun u. 10 Ati olori alufa ninu awọn arakunrin rẹ̀, ori ẹniti a dà oróro itasori si, ti a si yàsọtọ lati ma wọ̀ aṣọ wọnni, ki o máṣe ṣi ibori rẹ̀, tabi ki o fà aṣọ rẹ̀ ya; 11 Ki o má si ṣe wọle tọ̀ okú kan lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀; 12 Bẹ̃ni ki o máṣe jade kuro ninu ibi mimọ́, bẹ̃ni ki o máṣe bà ibi mimọ́ Ọlọrun rẹ̀ jẹ́, nitoripe adé oróro itasori Ọlọrun rẹ̀ mbẹ lori rẹ̀: Emi li OLUWA. 13 Wundia ni ki o fẹ́ li aya fun ara rẹ̀. 14 Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀. 15 Bẹ̃ni ki o máṣe bà irú-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ninu awọn enia rẹ̀: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà a simimọ́. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, 17 Sọ fun Aaroni pe, Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ rẹ ni iran-iran wọn, ti o ní àbuku kan, ki o máṣe sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀. 18 Nitoripe gbogbo ọkunrin ti o ní àbuku, ki o máṣe sunmọtosi: ọkunrin afọju, tabi amukun, tabi arẹ́mu, tabi ohun kan ti o leke, 19 Tabi ọkunrin ti iṣe aṣẹ́sẹ̀, tabi aṣẹ́wọ, 20 Tabi abuké, tabi arará, tabi ẹniti o ní àbuku kan li oju rẹ̀, tabi ti o ní ekuru, tabi ipẹ́, tabi ti kóro rẹ̀ fọ́; 21 Ẹnikẹni ti o ní àbuku ninu irúọmọ Aaroni alufa kò gbọdọ sunmọtosi lati ru ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: on li àbuku; kò gbọdọ sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀. 22 On o ma jẹ àkara Ọlọrun rẹ̀, ti mimọ́ julọ ati ti mimọ́. 23 Kìki on ki yio wọ̀ inu aṣọ-ikele nì lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sunmọ pẹpẹ, nitoriti on ní àbuku; ki on ki o máṣe bà ibi mimọ́ mi jẹ́: nitori Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. 24 Mose si wi fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli.

Lefitiku 22

Àwọn Ohun Ìrúbọ Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA, 3 Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA. 4 Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade; 5 Tabi ẹniti o ba farakàn ohun ti nrakò kan, ti yio sọ ọ di aimọ́, tabi enia kan ti yio sọ ọ di aimọ́, irú aimọ́ ti o wù ki o ní; 6 Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀. 7 Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni. 8 On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA. 9 Nitorina ki nwọn ki o ma pa ìlana mi mọ́, ki nwọn ki o máṣe rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nwọn a si kú nitorina, bi nwọn ba bà a jẹ́: Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. 10 Alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́: alabagbé alufa, tabi alagbaṣe kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́ na. 11 Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀. 12 Bi ọmọbinrin alufa na ba si ní alejò kan li ọkọ, obinrin na kò le jẹ ninu ẹbọ fifì ohun mimọ́. 13 Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀. 14 Bi ẹnikan ba si jẹ ninu ohun mimọ́ li aimọ̀, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun alufa pẹlu ohun mimọ́ na. 15 Nwọn kò si gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ti nwọn mú fun OLUWA wá: 16 Tabi lati jẹ ki nwọn ki o rù aiṣedede ti o mú ẹbi wá, nigbati nwọn ba njẹ ohun mimọ́ wọn: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. 17 OLUWA si sọ fun Mose pe, 18 Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu awọn alejò ni Israeli, ti o ba fẹ́ ru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ nitori ẹjẹ́ wọn gbogbo, ati nitori ẹbọ rẹ̀ atinuwá gbogbo, ti nwọn nfẹ́ ru si OLUWA fun ẹbọ sisun; 19 Ki o le dà fun nyin, akọ alailabùkun ni ki ẹnyin ki o fi ru u, ninu malu, tabi ninu agutan, tabi ninu ewurẹ. 20 Ṣugbọn ohunkohun ti o ní abùku, li ẹnyin kò gbọdọ múwa: nitoripe ki yio dà fun nyin. 21 Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀. 22 Afọju, tabi fifàya, tabi eyiti a palara, tabi elegbo, elekuru, tabi oni-ipẹ́, wọnyi li ẹnyin kò gbọdọ fi rubọ si OLUWA, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fi ninu wọn ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA lori pẹpẹ. 23 Ibaṣe akọmalu tabi ọdọ-agutan ti o ní ohun ileke kan, tabi ohun abùku kan, eyinì ni ki iwọ ma fi ru ẹbọ ifẹ́-atinuwá; ṣugbọn fun ẹjẹ́ ki yio dà. 24 Ẹnyin kò gbọdọ mú eyiti kóro rẹ̀ fọ́, tabi ti a tẹ̀, tabi ti a ya, tabi ti a là, wá rubọ si OLUWA; ki ẹnyin máṣe e ni ilẹ nyin. 25 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ti ọwọ́ alejò rubọ àkara Ọlọrun nyin ninu gbogbo wọnyi; nitoripe ibàjẹ́ wọn mbẹ ninu wọn, abùku si mbẹ ninu wọn: nwọn ki yio dà fun nyin. 26 OLUWA si sọ fun Mose pe, 27 Nigbati a ba bi akọmalu kan, tabi agutan kan, tabi ewurẹ kan, nigbana ni ki o gbé ijọ meje lọdọ iya rẹ̀; ati lati ijọ́ kẹjọ ati titi lọ on o di itẹwọgbà fun ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 28 Ibaṣe abomalu tabi agutan, ẹnyin kò gbọdọ pa a ati ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ kanna. 29 Nigbati ẹnyin ba si ru ẹbọ ọpẹ́ si OLUWA, ẹ ru u ki o le dà. 30 Li ọjọ́ na ni ki a jẹ ẹ; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ́kù silẹ ninu rẹ̀ titi di ijọ́ keji: Emi li OLUWA. 31 Nitorina ni ki ẹnyin ki o ma pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA. 32 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bà orukọ mimọ́ mi jẹ́; bikoṣe ki a yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́, 33 Ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi li OLUWA.

Lefitiku 23

Àwọn Àjọ̀dún Ẹ̀sìn

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, ajọ OLUWA, ti ẹnyin o pè fun apejọ mimọ́, wọnyi li ajọ mi. 3 Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ: ṣugbọn ni ijọ́ keje li ọjọ́ isimi, apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ kan ninu rẹ̀: nitoripe ọjọ́-isimi OLUWA ni ninu ibujoko nyin gbogbo. 4 Wọnyi li ajọ OLUWA, ani apejọ mimọ́, ti ẹnyin o pè li akokò wọn.

Àjọ̀dún Ìrékọjá ati Àìwúkàrà

5 Ni ijọ́ kẹrinla oṣù kini, li aṣalẹ, li ajọ irekọja OLUWA. 6 Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na li ajọ àkara alaiwu si OLUWA: ijọ́ meje li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu. 7 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara ninu rẹ̀. 8 Bikoṣe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni ijọ́ meje: ni ijọ́ keje ni apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara. 9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, ti ẹnyin o si ma ṣe ikore rẹ̀, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ìdi-ọkà kan akọ́so ikore nyin tọ̀ alufa wá: 11 On o si fì ìdi-ọkà na niwaju OLUWA, lati ṣe itẹwọgbà fun nyin: ni ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi ni ki alufa ki o fì i. 12 Li ọjọ́ ti ẹnyin fì ìdi-ọkà ni ki ẹnyin ki o rubọ akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan alailabùku fun ẹbọ sisun si OLUWA. 13 Ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ ki o jẹ́ meji idamẹwa òṣuwọn iyẹfun daradara, ti a fi oróro pò, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA fun õrun didùn: ati ẹbọ ohun-mimu rẹ̀ ni ki o ṣe ọtí-waini idamẹrin òṣuwọn hini. 14 Ẹnyin kò si gbọdọ jẹ àkara, tabi ọkà yiyan, tabi ọkà tutù ninu ipẹ́, titi yio fi di ọjọ́ na gan ti ẹnyin mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ Ọlọrun nyin wá: ki o si jasi ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.

Àjọ̀dún Ìkórè

15 Lati ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi, ni ọjọ́ ti ẹnyin mú ìdi-ọkà ẹbọ fifì nì wá, ki ẹnyin ki o si kà ọjọ́-isimi meje pé; 16 Ani di ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi keje, ki ẹnyin ki o kà ãdọta ọjọ́; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ titun si OLUWA. 17 Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA. 18 Pẹlu àkara na ki ẹnyin ki o si fi ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabukù rubọ, ati ẹgbọrọ akọmalu kan, ati àgbo meji: ki nwọn ki o jẹ́ ẹbọ sisun si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe olõrùn didùn ni si OLUWA. 19 Nigbana ni ki ẹnyin ki o fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan ru ẹbọ alafia. 20 Ki alufa ki o si fi wọn pẹlu àkara àwọn akọ́so fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA, pẹlu ọdọ-agutan meji nì: ki nwọn ki o si jẹ́ mimọ́ si OLUWA fun alufa na. 21 Ki ẹnyin ki o si kede li ọjọ́ na gan; ki o le jẹ́ apejọ mimọ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: yio si ma ṣe ìlana fun nyin titilai ni ibujoko nyin gbogbo ni iran-iran nyin. 22 Nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa ẹba oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pèṣẹ́ ikore rẹ̀: ki iwọ ki o fi i silẹ fun awọn talaka, ati fun alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Àjọ̀dún Ọdún Titun

23 OLUWA si sọ fun Mose pe, 24 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù ni ki ẹnyin ki o ní isimi; iranti ifunpe, apejọ mimọ́. 25 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: bikoṣepe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

Ọjọ́ Ètùtù

26 OLUWA si sọ fun Mose pe, 27 Ijọ́ kẹwa oṣù keje yi ni ki o ṣe ọjọ́ ètutu: ki apejọ mimọ́ wà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹ si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 28 Ẹnyin kò si gbọdọ ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi: nitoripe ọjọ́ ètutu ni, lati ṣètutu fun nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin. 29 Nitoripe ọkànkọkàn ti kò ba pọ́n ara rẹ̀ loju li ọjọ́ na yi, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 30 Ati ọkànkọkan ti o ba ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi, ọkàn na li emi o run kuro lãrin awọn enia rẹ̀. 31 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: ki o jẹ́ ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo. 32 Ọjọ́-isimi ni fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọn ọkàn nyin loju: lo ọjọ́ kẹsan oṣù na li alẹ, lati alẹ dé alẹ, ni ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́-isimi nyin mọ́.

Àjọ Àgọ́

33 OLUWA si sọ fun Mose pe, 34 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ kẹdogun oṣù keje yi li ajọ agọ́ ni ijọ́ meje si OLUWA. 35 Li ọjọ́ kini li apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan. 36 Ijọ meje ni ki ẹnyin fi ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ni ijọ́ kẹjọ li apejọ́ mimọ́ fun nyin; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọjọ́ ajọ ni; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan. 37 Wọnyi li ajọ OLUWA, ti ẹnyin o kedé lati jẹ́ apejọ mimọ́, lati ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ, ẹbọ, ati ẹbọ ohunmimu, olukuluku wọn li ọjọ́ rẹ̀: 38 Pẹlu ọjọ́-isimi OLUWA, ati pẹlu ẹ̀bun nyin, ati pẹlu gbogbo ẹjẹ́ nyin, ati pẹlu gbogbo ẹbọ atinuwá nyin ti ẹnyin fi fun OLUWA. 39 Pẹlupẹlu li ọjọ́ kẹdogun oṣù keje na, nigbati ẹnyin ba ṣe ikore eso ilẹ tán, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ si OLUWA ni ijọ́ meje: li ọjọ́ kini ki isimi ki o wà, ati li ọjọ́ kẹjọ ki isimi ki o wà, 40 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o si mú eso igi daradara, imọ̀-ọpẹ, ati ẹká igi ti o bò, ati ti igi wilo odò; ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin ni ijọ́ meje. 41 Ki ẹnyin ki o si ma pa a mọ́ li ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje li ọdún: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin: ki ẹnyin ki o ma ṣe e li oṣù keje. 42 Ki ẹnyin ki o ma gbé inu agọ́ ni ijọ́ meje; gbogbo ibilẹ ni Israeli ni ki o gbé inu agọ́: 43 Ki iran-iran nyin ki o le mọ̀ pe, Emi li o mu awọn ọmọ Israeli gbé inu agọ́, nigbati mo mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 44 Mose si sọ gbogbo ajọ OLUWA wọnyi fun awọn ọmọ Israeli.

Lefitiku 24

Ìtọ́jú Àwọn Fìtílà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú oróro daradara ti olifi gigún fun ọ wá, fun imọlẹ lati ma mu fitila jó nigbagbogbo. 3 Lẹhin ode aṣọ-ikele ẹrí, ninu agọ́ ajọ, ni ki Aaroni ki o tọju rẹ̀ lati aṣalẹ di owurọ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin. 4 Ki o si tọju fitila lori ọpá-fitila mimọ́ nì nigbagbogbo niwaju OLUWA.

Àkàrà Tí Wọ́n Fi Rúbọ sí Ọlọrun

5 Ki iwọ ki o si mú iyẹfun daradara, ki o si yan ìṣu-àkara mejila ninu rẹ̀: idamẹwa meji òṣuwọn ni ki o wà ninu ìṣu-àkara kan. 6 Ki iwọ ki o si tò wọn li ẹsẹ meji, mẹfa li ẹsẹ kan, lori tabili mimọ́ niwaju OLUWA. 7 Ki iwọ ki o si fi turari daradara sori ẹsẹ̀ kọkan ki o le wà lori ìṣu-àkara na fun iranti, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 8 Li ọjọjọ́ isimi ni ki ẹ ma tun u tò niwaju OLUWA titi; gbigbà ni lọwọ awọn ọmọ Israeli nipa majẹmu titi aiye. 9 Ki o si ma jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ; ki nwọn ki o si ma jẹ ẹ ni ibi mimọ́ kan: nitoripe mimọ́ julọ ni fun u ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ìlana titilai.

Àpẹẹrẹ Ìdájọ́ ati Ìjẹníyà Tí Ó Tọ́

10 Ati ọmọkunrin obinrin Israeli kan, ti baba rẹ̀ ṣe ara Egipti, o jade lọ ninu awọn ọmọ Israeli: ọmọkunrin obinrin Israeli yi ati ọkunrin Israeli kan si jà ni ibudó. 11 Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani. 12 Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn. 13 OLUWA si sọ fun Mose pe, 14 Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta. 15 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ti o ba fi Ọlọrun rẹ̀ bú yio rù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16 Ati ẹniti o sọ̀rọ buburu si orukọ OLUWA nì, pipa ni ki a pa a: gbogbo ijọ enia ni ki o sọ ọ li okuta pa nitõtọ: ati alejò, ati ibilẹ, nigbati o ba sọ̀rọbuburu si orukọ OLUWA, pipa li a o pa a. 17 Ati ẹniti o ba gbà ẹmi enia, pipa li a o pa a: 18 Ẹniti o ba si lù ẹran kan pa, ki o san a pada: ẹmi fun ẹmi. 19 Bi ẹnikan ba si ṣe abùku kan si ara ẹnikeji rẹ̀; bi o ti ṣe, bẹ̃ni ki a ṣe si i; 20 Ẹ̀ya fun ẹ̀ya, oju fun oju, ehin fun ehin; bi on ti ṣe abùku si ara enia, bẹ̃ni ki a ṣe si i. 21 Ẹniti o ba si lù ẹran pa, ki o san a pada: ẹniti o ba si lù enia pa, a o pa a. 22 Irú ofin kan li ẹnyin o ní, gẹgẹ bi fun alejò bẹ̃ni fun ibilẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 23 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, pe ki nwọn ki o mú ẹniti o ṣe ifibu nì jade lọ sẹhin ibudó, ki nwọn ki o si sọ ọ li okuta pa. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Lefitiku 25

Ọdún Keje

1 OLUWA si sọ fun Mose li òke Sinai pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, nigbana ni ki ilẹ na ki o pa isimi kan mọ́ fun OLUWA. 3 Ọdún mẹfa ni iwọ o fi gbìn oko rẹ, ọdún mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgbà-ajara rẹ, ti iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ; 4 Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ. 5 Eyiti o ba lalẹ̀ hù ninu ikore rẹ iwọ kò gbọdọ ká, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká eso àjara rẹ ti iwọ kò rẹ́ lọwọ: nitoripe ọdún isimi ni fun ilẹ na. 6 Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ; 7 Ati fun ohunọ̀sin rẹ, ati fun ẹran ti mbẹ ni ilẹ rẹ, ni ki ibisi rẹ̀ gbogbo ki o ṣe onjẹ fun.

Ọdún Ìdásílẹ̀ ati Ìdápadà

8 Ki iwọ ki o si kà ọdún isimi meje fun ara rẹ, ọdún meje ìgba meje; ati akokò ọdún isimi meje ni yio jẹ́ ọdún mọkandilãdọta fun ọ. 9 Ki iwọ ki o si mu ki ipè ki o dún ni ijọ́ kẹwa oṣù keje, li ọjọ́ ètutu ni ki ẹnyin ki o mu ipè na dún ni gbogbo ilẹ nyin. 10 Ki ẹnyin ki o si yà arãdọta ọdún simimọ́, ki ẹnyin ki o si kede idasilẹ ni ilẹ na fun gbogbo awọn ti ngbé inu rẹ̀: yio si ma jẹ́ jubeli fun nyin; ki ẹnyin ki o si pada olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si pada sinu idile rẹ̀. 11 Ọdún jubeli ni ki arãdọta ọdún ki o jasi fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká ilalẹ-hù inu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká eso àjara rẹ̀ ti a kò rẹ-lọwọ. 12 Nitoripe jubeli ni; mimọ́ ni ki o jasi fun nyin: ibisi rẹ̀ ni ki ẹnyin o ma jẹ lati inu oko wa. 13 Li ọdún jubeli yi ni ki olukuluku nyin ki o pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. 14 Bi iwọ ba si tà ọjà fun ẹnikeji rẹ, tabi bi iwọ ba rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ: 15 Gẹgẹ bi iye ọdún lẹhin jubeli ni ki iwọ ki o rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ati gẹgẹ bi iye ọdún ikore rẹ̀ ni ki o tà fun ọ. 16 Gẹgẹ bi ọ̀pọ ọdún ni ki iwọ ki o bù owo rẹ̀ sí i, ati gẹgẹ bi ọdún rẹ̀ ti fàsẹhin, ni ki iwọ ki o si bù owo rẹ̀ kù; nitoripe gẹgẹ bi iye ọdún ikore ni ki o tà fun ọ. 17 Nitorina ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ; bikoṣe pe ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Ìyọnu Tí Ó Wà ninu Ọdún Keje

18 Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu. 19 Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu. 20 Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa: 21 Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta. 22 Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ.

Dídá Nǹkan Ìní Pada

23 Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi. 24 Ati ni gbogbo ilẹ-iní nyin ki ẹnyin ki o si ma ṣe ìrapada fun ilẹ. 25 Bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti o ba si tà ninu ilẹ-iní rẹ̀, bi ẹnikan ninu awọn ibatan rẹ̀ ba si wá lati rà a, njẹ ki o rà eyiti arakunrin rẹ̀ ti tà pada. 26 Bi ọkunrin na kò ba ní ẹnikan ti yio rà a pada, ti on tikara rẹ̀ ti di olowo ti o ní to lati rà a pada; 27 Nigbana ni ki o kà ọdún ìta rẹ̀, ki o si mú elé owo rẹ̀ pada fun ẹniti o tà a fun, ki on ki o le pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. 28 Ṣugbọn bi o ba ṣepe on kò le san a pada fun u, njẹ ki ohun ti o tà na ki o gbé ọwọ́ ẹniti o rà a titi di ọdún jubeli: yio si bọ́ ni jubeli, on o si pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀. 29 Bi ọkunrin kan ba si tà ile gbigbé kan ni ilu olodi, njẹ ki o rà a pada ni ìwọn ọdún kan lẹhin ti o tà a; ni ìwọn ọdún kan ni ki o rà a pada. 30 Bi a kò ba si rà a ni ìwọn ọdún kan gbako, njẹ ki ile na ki o di ti ẹniti o rà a titilai ni iran-iran rẹ̀: ki yio bọ́ ni jubeli. 31 Ṣugbọn ile ileto wọnni ti kò ni odi yi wọn ká awọn li a kà si ibi oko ilu: ìrapada li awọn wọnni, nwọn o si bọ́ ni jubeli. 32 Ṣugbọn niti ilu awọn ọmọ Lefi, ile ilu iní wọn, ni awọn ọmọ Lefi o ma ràpada nigbakugba. 33 Bi ẹnikan ba si rà lọwọ awọn ọmọ Lefi, njẹ ile ti a tà na, ni ilu iní rẹ̀, ki o bọ́ ni jubeli: nitoripe ile ilu awọn ọmọ Lefi ni ilẹ-iní wọn lãrin awọn ọmọ Israeli. 34 Ṣugbọn ilẹ ẹba ilu wọn ni nwọn kò gbọdọ tà; nitoripe ilẹ-iní wọn ni titi aiye.

Yíyá Aláìní Lówó

35 Ati bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti ọwọ́ rẹ̀ ba si rẹlẹ lọdọ rẹ; njẹ ki iwọ ki o ràn a lọwọ; ibaṣe alejò, tabi atipo; ki on ki o le wà pẹlu rẹ. 36 Iwọ máṣe gbà elé lọwọ rẹ̀, tabi ẹdá; ṣugbọn bẹ̀ru Ọlọrun rẹ; ki arakunrin rẹ ki o le wà pẹlu rẹ. 37 Iwọ kò gbọdọ fi owo rẹ fun u li ẹdá, tabi ki o wín i li onjẹ rẹ fun asanlé. 38 Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, lati fi ilẹ Kenaani fun nyin, ati lati ma ṣe Ọlọrun nyin.

Ìdásílẹ̀ Àwọn Ẹrú

39 Ati bi arakunrin rẹ ti mba ọ gbé ba di talakà, ti o si tà ara rẹ̀ fun ọ; iwọ kò gbọdọ sìn i ni ìsin-ẹrú: 40 Bikoṣe bi alagbaṣe, ati bi atipo, ni ki o ma ba ọ gbé, ki o si ma sìn ọ titi di ọdún jubeli: 41 Nigbana ni ki o lọ kuro lọdọ rẹ, ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ki o si pada lọ si idile rẹ̀, ati si ilẹ-iní awọn baba rẹ̀ ni ki o pada si. 42 Nitoripe iranṣẹ mi ni nwọn iṣe, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: a kò gbọdọ tà wọn bi ẹni tà ẹrú. 43 Iwọ kò gbọdọ fi irorò sìn i; ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ. 44 Ati awọn ẹrú rẹ ọkunrin, ati awọn ẹrú rẹ obinrin, ti iwọ o ní; ki nwọn ki o jẹ́ ati inu awọn orilẹ-ède wá ti o yi nyin ká, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o ma rà awọn ẹrú-ọkunrin ati awọn ẹrú-obinrin. 45 Pẹlupẹlu ninu awọn ọmọ alejò ti nṣe atipo pẹlu nyin, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o rà, ati ninu awọn idile wọn ti mbẹ pẹlu nyin, ti nwọn bi ni ilẹ nyin: nwọn o si jẹ iní nyin. 46 Ẹnyin o si ma fi wọn jẹ ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin, lati ní wọn ni iní; ẹnyin o si ma sìn wọn lailai: ṣugbọn ninu awọn arakunrin nyin awọn ọmọ Israeli, ẹnikan kò gbọdọ fi irorò sìn ẹnikeji rẹ̀. 47 Ati bi alejò tabi atipo kan ba di ọlọrọ̀ lọdọ rẹ, ati arakunrin rẹ kan leti ọdọ rẹ̀ ba di talakà, ti o ba si tà ara rẹ̀ fun alejò tabi atipo na leti ọdọ rẹ, tabi fun ibatan idile alejò na: 48 Lẹhin igbati o tà ara rẹ̀ tán, a si tún le rà a pada; ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀ le rà a: 49 Ibaṣe arakunrin õbi rẹ̀, tabi ọmọ arakunrin õbi rẹ̀, le rà a, tabi ibatan rẹ̀ ninu idile rẹ̀ le rà a; tabi bi o ba di ọlọrọ̀, o le rà ara rẹ̀. 50 Ki o si ba ẹniti o rà a ṣìro lati ọdún ti o ti tà ara rẹ̀ fun u titi di ọdún jubeli: ki iye owo ìta rẹ̀ ki o si ri gẹgẹ bi iye ọdún, gẹgẹ bi ìgba alagbaṣe ni ki o ri fun u. 51 Bi ọdún rẹ̀ ba kù pupọ̀ sibẹ̀, gẹgẹ bi iye wọn ni ki o si san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada ninu owo ti a fi rà a. 52 Bi o ba si ṣepe kìki ọdún diẹ li o kù titi di ọdún jubeli, njẹ ki o ba a ṣìro, gẹgẹ bi iye ọdún rẹ̀ ni ki o san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada. 53 Bi alagbaṣe ọdọdún ni ki o ma ba a gbé: ki on ki o máṣe fi irorò sìn i li oju rẹ. 54 Bi a kò ba si fi wọnyi rà a silẹ, njẹ ki o jade lọ li ọdún jubeli, ati on, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 55 Nitoripe iranṣẹ mi li awọn ọmọ Israeli iṣe; iranṣẹ mi ni nwọn ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

Lefitiku 26

Ibukun fún Ìgbọràn

1 ẸNYIN kò gbọdọ yá oriṣa, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ gbé ere tabi ọwọ̀n kan dide naró fun ara nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ gbé ere okuta gbigbẹ kalẹ ni ilẹ nyin, lati tẹriba fun u: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 2 Ki ẹnyin ki o pa ọjọ́-isimi mi mọ́, ki ẹ si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA. 3 Bi ẹnyin ba nrìn ninu ìlana mi, ti ẹ si npa ofin mi mọ́, ti ẹ si nṣe wọn; 4 Nigbana li emi o fun nyin li òjo li akokò rẹ̀, ilẹ yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, igi oko yio si ma so eso wọn. 5 Ipakà nyin yio si dé ìgba ikore àjara, igba ikore àjara yio si dé ìgba ifunrugbìn: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu. 6 Emi o si fi alafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si sí ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹ̃ni idà ki yio là ilẹ nyin já. 7 Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin. 8 Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin. 9 Nitoriti emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ̀, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin. 10 Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun. 11 Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin. 12 Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi. 13 Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

14 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, ti ẹ kò si ṣe gbogbo ofin wọnyi; 15 Bi ẹnyin ba si gàn ìlana mi, tabi bi ọkàn nyin ba korira idajọ mi, tobẹ̃ ti ẹnyin ki yio fi ṣe gbogbo ofin mi, ṣugbọn ti ẹnyin dà majẹmu mi; 16 Emi pẹlu yio si ṣe eyi si nyin; emi o tilẹ rán ẹ̀ru si nyin, àrun-igbẹ ati òjojo gbigbona, ti yio ma jẹ oju run, ti yio si ma mú ibinujẹ ọkàn wá: ẹnyin o si fun irugbìn nyin lasan, nitoripe awọn ọtá nyin ni yio jẹ ẹ. 17 Emi o si kọ oju mi si nyin, a o si pa nyin niwaju awọn ọtá nyin: awọn ti o korira nyin ni yio si ma ṣe olori nyin; ẹnyin o si ma sá nigbati ẹnikan kò lé nyin. 18 Ninu gbogbo eyi, bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, nigbana li emi o jẹ nyin ni ìya ni ìgba meje si i nitori ẹ̀ṣẹ nyin. 19 Emi o si ṣẹ́ igberaga agbara nyin; emi o si sọ ọrun nyin dabi irin, ati ilẹ nyin dabi idẹ: 20 Ẹnyin o si lò agbara nyin lasan: nitoriti ilẹ nyin ki yio mú ibisi rẹ̀ wá, bẹ̃ni igi ilẹ nyin ki yio so eso wọn. 21 Bi ẹnyin ba si nrìn lodi si mi, ti ẹnyin kò si gbọ́ ti emi; emi o si mú iyọnu ìgba meje wá si i lori nyin gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ nyin. 22 Emi o si rán ẹranko wá sinu nyin pẹlu, ti yio ma gbà nyin li ọmọ, ti yio si ma run nyin li ẹran-ọ̀sin, ti yio si mu nyin dinkù; opópo nyin yio si dahoro. 23 Bi ẹnyin kò ba gbà ìkilọ mi nipa nkan wọnyi, ṣugbọn ti ẹnyin o ma rìn lodi si mi; 24 Nigbana li emi pẹlu yio ma rìn lodi si nyin, emi o si jẹ nyin ni ìya si i ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin. 25 Emi o si mú idà wá sori nyin, ti yio gbà ẹsan majẹmu mi; a o si kó nyin jọ pọ̀ ninu ilu nyin, emi o rán ajakalẹ-àrun sãrin nyin; a o si fi nyin lé ọtá lọwọ. 26 Nigbati mo ba ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin, obinrin mẹwa yio yan àkara nyin ninu àro kan, ìwọ̀n ni nwọn o si ma fi fun nyin li àkara nyin: ẹnyin o si ma jẹ, ẹ ki yio si yó. 27 Ninu gbogbo eyi bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, ti ẹ ba si nrìn lodi si mi; 28 Nigbana li emi o ma rìn lodi si nyin pẹlu ni ikannu; emi pẹlu yio si nà nyin ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin. 29 Ẹnyin o si jẹ ẹran-ara awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati ẹran-ara awọn ọmọ nyin obinrin li ẹnyin o jẹ. 30 Emi o si run ibi giga nyin wọnni, emi o si ke ere nyin lulẹ, emi o si wọ́ okú nyin sori okú oriṣa nyin; ọkàn mi yio si korira nyin. 31 Emi o si sọ ilu nyin di ahoro, emi o si sọ ibi mimọ́ nyin di ahoro, emi ki yio gbọ́ adùn õrùn didùn nyin mọ́. 32 Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si yà awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ̀ si i. 33 Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà tì nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro. 34 Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀. 35 Ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ́-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ̀. 36 Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa. 37 Nwọn o si ma ṣubulù ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò sí ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si lí agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin. 38 Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ. 39 Ati awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹ̀ṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹ̀ṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn. 40 Bi nwọn ba si jẹwọ irekọja wọn, ati irekọja awọn baba wọn, pẹlu ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, ati pẹlu nitoripe nwọn ti rìn lodi si mi; 41 Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn; 42 Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na. 43 Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi. 44 Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn: 45 Ṣugbọn nitori wọn emi o ranti majẹmu awọn baba nla wọn, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá li oju awọn orilẹ-ède, ki emi ki o le ma ṣe Ọlọrun wọn: Emi li OLUWA. 46 Wọnyi ni ìlana ati idajọ, ati ofin ti OLUWA dásilẹ, lãrin on ati awọn ọmọ Israeli li òke Sinai nipa ọwọ́ Mose.

Lefitiku 27

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Ohun tí a fi fún OLUWA

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ. 3 Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́. 4 Bi on ba si ṣe obinrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ọgbọ̀n ṣekeli. 5 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa. 6 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta. 7 Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa. 8 Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e. 9 Bi o ba si ṣepe ẹran ni, ninu eyiti enia mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ OLUWA wá, gbogbo eyiti ẹnikẹni ba múwa ninu irú nkan wọnni fun OLUWA ki o jẹ́ mimọ́. 10 On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́. 11 Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa: 12 Ki alufa ki o si diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi iwọ alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. 13 Ṣugbọn bi o ba fẹ́ rà a pada rára, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ kún idiyelé rẹ. 14 Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. 15 Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. 16 Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà. 17 Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri. 18 Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ. 19 Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. 20 Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́. 21 Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa. 22 Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún; 23 Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA. 24 Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe. 25 Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan. 26 Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni. 27 Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ. 28 Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA. 29 Kò sí ẹni ìyasọtọ ti a ba yàsọtọ ninu enia, ti a le gbàsilẹ; pipa ni ki a pa a. 30 Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA. 31 Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u. 32 Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA. 33 Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada. 34 Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.

Numeri 1

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe, 2 Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn; 3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn. 4 Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀. 5 Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 6 Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. 7 Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu. 8 Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari. 9 Ti Sebuluni; Eliabu ọmọ Heloni. 10 Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru. 11 Ti Benjamini; Abidani ọmọ Gideoni. 12 Ti Dani; Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 13 Ti Aṣeri; Pagieli ọmọ Okanri. 14 Ti Gadi; Eliasafu ọmọ Deueli. 15 Ti Naftali; Ahira ọmọ Enani. 16 Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli. 17 Ati Mose ati Aaroni mú awọn ọkunrin wọnyi ti a pè li orukọ: 18 Nwọn si pè gbogbo ijọ enia pọ̀ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si pìtan iran wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ori wọn. 19 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li o si kaye wọn ni ijù Sinai. 20 Ati awọn ọmọ Reubeni, akọ́bi Israeli, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 21 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Reubeni, o jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta. 22 Ti awọn ọmọ Simeoni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 23 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Simeoni, o jẹ́ ẹgba mọkandilọgbọ̀n o le ẹdegbeje. 24 Ti awọn ọmọ Gadi, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 25 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Gadi, o jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ. 26 Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 27 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Juda, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilogoji o le ẹgbẹ̀ta. 28 Ti awọn ọmọ Issakari, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 29 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Issakari, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo. 30 Ti awọn ọmọ Sebuluni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 31 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Sebuluni, o jẹ́ ẹgbã mejidilọgbọ̀n o le egbeje. 32 Ti awọn ọmọ Josefu, eyinì ni, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 33 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Efraimu, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 34 Ti awọn ọmọ Manasse, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 35 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Manasse, o jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba. 36 Ti awọn ọmọ Benjamini, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 37 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Benjamini, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje. 38 Ti awọn ọmọ Dani, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 39 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Dani, o jẹ́ ẹgbã mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 40 Ti awọn ọmọ Aṣeri, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 41 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Aṣeri, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ. 42 Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 43 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Naftali, o jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. 44 Wọnyi li awọn ti a kà, ti Mose ati Aaroni kà, ati awọn olori Israeli, ọkunrin mejila: olukuluku wà fun ile awọn baba rẹ̀. 45 Bẹ̃ni gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli, nipa ile baba wọn, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli; 46 Ani gbogbo awọn ti a kà o jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ enia o le egbejidilogun din ãdọta. 47 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ẹ̀ya baba wọn li a kò kà mọ́ wọn. 48 Nitoripe OLUWA ti sọ fun Mose pe, 49 Kìki ẹ̀ya Lefi ni ki iwọ ki o máṣe kà, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe kà iye wọn mọ́ awọn ọmọ Israeli. 50 Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká. 51 Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni. 52 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si pa agọ́ wọn, olukuluku ni ibudó rẹ̀, ati olukuluku lẹba ọpagun rẹ̀, gẹgẹ bi ogun wọn. 53 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na. 54 Bayi ni awọn ọmọ Israeli si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.

Numeri 2

Ètò Pípa Àgọ́ Ní Ẹlẹ́yà-mẹ̀yà

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká. 3 Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda. 4 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le ẹgbẹta. 5 Ati awọn ti o pagọ́ gbè e ki o jẹ́ ẹ̀ya Issakari: Netaneli ọmọ Suari yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Issakari: 6 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo. 7 Ati ẹ̀ya Sebuluni: Eliabu ọmọ Heloni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Sebuluni: 8 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejidilọgbọ̀n o le egbeje. 9 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Juda jẹ́ ẹgba mẹtalelãdọrun o le irinwo, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn yi ni yio kọ́ ṣí. 10 Ni ìha gusù ni ki ọpagun ibudó Reubeni ki o wà, gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuru ọmọ Ṣedeuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Reubeni: 11 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta. 12 Ati awọn ti o pagọ́ tì i ki o jẹ́ ẹ̀ya Simeoni: Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Simeoni: 13 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkandilọgbòn o le ẹdegbeje. 14 Ati ẹ̀ya Gadi: Eliasafu ọmọ Deueli ni yio si jẹ́ olori ogun ti awọn ọmọ Gadi: 15 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ. 16 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji. 17 Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn. 18 Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu: 19 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 20 Ati lẹba rẹ̀ ni ki ẹ̀ya Manasse ki o wà: Gamalieli ọmọ Pedahsuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Manasse: 21 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba. 22 Ati ẹ̀ya Benjamini: Abidani ọmọ Gideoni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Benjamini: 23 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje. 24 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Efraimu, jẹ́ ẹgba mẹrinlelãdọta o le ọgọrun, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikẹta. 25 Ọpagun ibudó Dani ni ki o wà ni ìha ariwa gẹgẹ bi ogun wọn: Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Dani. 26 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 27 Ati awọn ti o dó tì i ni ki o jẹ́ ẹ̀ya Aṣeri: Pagieli ọmọ Okrani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Aṣeri: 28 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ. 29 Ati ẹ̀ya Naftali: Ahira ọmọ Enani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Naftali: 30 Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. 31 Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Dani, jẹ́ ẹgba mejidilọgọrin o le ẹgbẹjọ. Awọn ni yio ṣí kẹhin pẹlu ọpagun wọn. 32 Eyi li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ile baba wọn: gbogbo awọn ti a kà ni ibudó gẹgẹ bi ogun wọn, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ o le egbejidilogun din ãdọta. 33 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi li a kò kà mọ́ awọn ọmọ Israeli; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 34 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.

Numeri 3

Àwọn Ọmọ Aaroni

1 WỌNYI si li awọn iran Aaroni ati Mose li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ li òke Sinai. 2 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Aaroni; Nadabu akọ́bi, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari. 3 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa. 4 Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.

Wọ́n yan Àwọn Ọmọ Lefi láti máa ṣe Iranṣẹ fún Àwọn Àlùfáà

5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u. 7 Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́. 8 Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́. 9 Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli. 10 Ki iwọ ki o si yàn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma duro si iṣẹalufa wọn: alejò ti o ba si sunmọtosi pipa ni ki a pa a. 11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe: 13 Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.

Kíka Àwọn Ọmọ Lefi

14 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai pe, 15 Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn. 16 Mose si kà wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, bi a ti paṣẹ fun u. 17 Wọnyi si ni awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi orukọ wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari. 18 Wọnyi si ni orukọ awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn; Libni ati Ṣimei. 19 Ati awọn ọmọ Kohati gẹgẹ bi idile wọn: Amramu, ati Ishari, Hebroni, ati Usieli. 20 Ati awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn; Mali, ati Muṣi. Wọnyi ni awọn idile Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn. 21 Ti Gerṣoni ni idile awọn ọmọ Libni, ati idile awọn ọmọ Ṣimei; wọnyi ni idile awọn ọmọ Gerṣoni. 22 Awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani iye awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbata o le ẹdẹgbẹjọ. 23 Awọn idile awọn ọmọ Gerṣoni ni ki o dó lẹhin agọ́ ni ìha ìwọ-õrùn. 24 Ati Eliasafu ọmọ Laeli ni ki o ṣe olori ile baba awọn ọmọ Gerṣoni. 25 Ati itọju awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ ni, Agọ́, ibori rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ti ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, 26 Ati aṣọ isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọtita ti ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́, ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn rẹ̀ fun gbogbo iṣẹ-ìsin rẹ̀. 27 Ati ti Kohati ni idile awọn ọmọ Amramu, ati idile ti awọn ọmọ Ishari, ati idile ti awọn ọmọ Hebroni, ati idile ti awọn ọmọ Usieli: wọnyi ni idile awọn ọmọ Kohati. 28 Gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrin o le ẹgbẹta, ti nṣe itọju ibi-mimọ́. 29 Awọn idile ti awọn ọmọ Kohati ni ki o pagọ́ lẹba agọ́ si ìha gusù. 30 Ati Elisafani ọmọ Usieli ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile awọn ọmọ Kohati. 31 Apoti, ati tabeli, ati ọpá-fitila, ati pẹpẹ wọnni, ati ohun-èlo ibi-mimọ́, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ alufa, ati aṣọ-tita, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin rẹ̀, ni yio jẹ́ ohun itọju wọn. 32 Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́. 33 Ti Merari ni idile awọn ọmọ Mali, ati idile awọn ọmọ Musi: wọnyi ni idile Merari. 34 Ati awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ọgbọkanlelọgbọ̀n. 35 Ati Surieli ọmọ Abihaili ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile Merari; ki nwọn ki o dó ni ìhà agọ́ si ìhà ariwa. 36 Iṣẹ itọju awọn ọmọ Merari yio si jẹ́ apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo ìsin rẹ̀; 37 Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn. 38 Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a. 39 Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni kà nipa aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi idile wọn, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mọkanla,

Àwọn Ọmọ Lefi Rọ́pò Àwọn Àkọ́bí

40 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kà gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin awọn ọmọ Israeli lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki o si gbà iye orukọ wọn. 41 Ki iwọ ki o si gbà awọn ọmọ Lefi fun mi (Emi li OLUWA) ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli; ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi, ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli. 42 Mose si kà gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, bi OLUWA ti paṣẹ fun u. 43 Ati gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin nipa iye orukọ, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ ninu eyiti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ọrinlugba o din meje. 44 OLUWA si sọ fun Mose pe, 45 Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA. 46 Ati fun ìrapada awọn ọrinlugba din meje ti awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ti nwọn fi jù awọn ọmọ Lefi lọ, 47 Ani ki o gbà ṣekeli marun-marun li ori ẹni kọkan, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́ ni ki o gbà wọn; (ogun gera ni ṣekeli kan): 48 Ki o si fi ninu owo na, ani owo ìrapada ti o lé ninu wọn, fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀. 49 Mose si gbà owo ìrapada lọwọ awọn ti o lé lori awọn ti a fi awọn ọmọ Lefi rasilẹ: 50 Lọwọ awọn akọ́bi awọn ọmọ Israeli li o gbà owo na; egbeje ṣekeli o din marundilogoji, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: 51 Mose si fi owo awọn ti a rapada fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Numeri 4

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi–Ìdílé Kohati

1 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, 2 Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn, 3 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. 4 Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni: 5 Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí; 6 Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ. 7 Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀: 8 Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. 9 Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀. 10 Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi. 11 Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. 12 Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi. 13 Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o. 14 Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. 15 Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ. 16 Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na. 17 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 18 Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi: 19 Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀; 20 Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi – Ìdílé Geriṣoni

21 OLUWA si sọ fun Mose pe, 22 Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn; 23 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. 24 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù: 25 Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ; 26 Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn. 27 Nipa aṣẹ Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ki gbogbo iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Gerṣoni jẹ́, ni gbogbo ẹrù wọn, ati ni gbogbo iṣẹ-ìsin wọn: ki ẹnyin si yàn wọn si itọju gbogbo ẹrù wọn. 28 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi – Ìdílé Merari

29 Ati awọn ọmọ Merari, ki iwọ ki o kà wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn; 30 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́. 31 Eyi si ni itọju ẹrù wọn, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin wọn ninu agọ́ ajo; awọn apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ìhò-ìtẹbọ rẹ̀, 32 Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn, pẹlu ohun-èlo wọn gbogbo, ati pẹlu ohun-ìsin wọn gbogbo: li orukọ li orukọ ni ki ẹnyin ki o kà ohun-èlo ti iṣe itọju ẹrù wọn. 33 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa.

Iye Àwọn Ọmọ Lefi

34 Mose ati Aaroni ati awọn olori ijọ awọn enia si kà awọn ọmọ Kohati nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, 35 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ: 36 Awọn ti a si kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrinla o din ãdọta. 37 Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Kohati, gbogbo awọn ti o le ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. 38 Awọn ti a si kà ninu awọn ọmọ Gerṣoni, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, 39 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ, 40 Ani awọn ti a kà ninu wọn, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, jẹ́ ẹgbẹtala o le ọgbọ̀n. 41 Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Gerṣoni, gbogbo awọn ti o ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA. 42 Awọn ti a si kà ni idile awọn ọmọ Merari, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, 43 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ, 44 Ani awọn ti a kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrindilogun. 45 Wọnyi li awọn ti a kà ninu idile awọn ọmọ Merari, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. 46 Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni ati awọn olori Israeli kà, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, 47 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wá lati ṣe iṣẹ-ìsin, ati iṣẹ ẹrù ninu agọ́ ajọ, 48 Ani awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbẹtalelẹgbarin o din ogun. 49 Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Numeri 5

Àwọn Aláìmọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o yọ gbogbo adẹ̀tẹ kuro ni ibudó, ati gbogbo ẹniti o ní isun, ati ẹnikẹni ti o di alaimọ́ nipa okú: 3 Ati ọkunrin ati obinrin ni ki ẹnyin ki o yọ kuro, lẹhin ode ibudó ni ki ẹ fi wọn si; ki nwọn ki o máṣe sọ ibudó wọn di alaimọ́, lãrin eyiti Emi ngbé. 4 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si yọ wọn sẹhin ibudó: bi OLUWA ti sọ fun Mose, bẹ̃ li awọn ọmọ Israeli ṣe.

Ìjìyà fún Ẹ̀ṣẹ̀

5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba dá ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ti enia ida, ti o ṣe irekọja si OLUWA, ti oluwarẹ̀ si jẹ̀bi; 7 Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀. 8 Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u. 9 Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀. 10 Ati ohun mimọ́ olukuluku, ki o jẹ́ tirẹ̀: ohunkohun ti ẹnikan ba fi fun alufa ki o jẹ́ tirẹ̀.

Àwọn Aya Tí Ọkọ Wọn Bá Fura sí

11 OLUWA si sọ fun Mose pe, 12 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi aya ọkunrin kan ba yapa, ti o si ṣẹ̀ ẹ, 13 Ti ọkunrin kan si bá a dàpọ, ti o si pamọ́ fun ọkọ rẹ̀, ti o si sin, ti on si di ẹni ibàjẹ́, ti kò si sí ẹlẹri kan si i, ti a kò si mú u mọ ọ, 14 Ti ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ti obinrin na si di ẹni ibàjẹ́: tabi bi ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ṣugbọn ti on kò di ẹni ibàjẹ́: 15 Nigbana ni ki ọkunrin na ki o mú aya rẹ́ tọ̀ alufa wá, ki o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun u, idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun barle; ki o máṣe dà oróro sori rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sinu rẹ̀; nitoripe ẹbọ ohunjijẹ owú ni, ẹbọ ohunjijẹ iranti ni, ti nmú irekọja wá si iranti. 16 Ki alufa na ki o si mú u sunmọtosi, ki o mu u duro niwaju OLUWA: 17 Ki alufa ki o si bù omi mimọ́ ninu ohun-èlo amọ̀ kan; ati ninu erupẹ ti mbẹ ni ilẹ agọ́ ni ki alufa ki o bù, ki o si fi i sinu omi na: 18 Ki alufa ki o si mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki o si ṣí ibori obinrin na, ki o si fi ẹbọ ohunjijẹ iranti na lé e li ọwọ́, ti iṣe ẹbọ ohunjijẹ owú: ati li ọwọ́ alufa ni omi kikorò ti imú egún wá yio wà. 19 Alufa na yio si mu u bura, yio si wi fun obinrin na pe, Bi ọkunrin kò ba bá ọ dàpọ, bi iwọ kò ba si yàsapakan si ìwa-aimọ́, labẹ ọkọ rẹ, ki iwọ ki o yege omi kikorò yi ti imú egún wá: 20 Ṣugbọn bi iwọ ba yapa, labẹ ọkọ rẹ, ti iwọ si di ẹni ibàjẹ́, ti ọkunrin miran si bá ọ dàpọ laiṣe ọkọ rẹ: 21 Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú; 22 Ati omi yi ti nmú egún wá ki o wọ̀ inu rẹ lọ, lati mu inu rẹ wú, ati lati mu itan rẹ rà: ki obinrin na ki o si wipe, Amin, amin. 23 Ki alufa ki o si kọ egún yi sinu iwé, ki o si fi omi kikorò na wẹ̀ ẹ nù: 24 Ki o si jẹ ki obinrin na ki o mu omi kikorò na ti imú egún wá: omi na ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò. 25 Nigbana li alufa yio gbà ẹbọ ohunjijẹ owú na li ọwọ́ obinrin na, yio si fì ẹbọ ohunjijẹ na niwaju OLUWA, yio si ru u lori pẹpẹ: 26 Ki alufa ki o si bù ikunwọ kan ninu ẹbọ ohunjijẹ na, ani iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ, lẹhin eyinì ki o jẹ ki obinrin na mu omi na. 27 Nigbati o ba si mu omi na tán, yio si ṣe, bi o ba ṣe ẹni ibàjẹ́, ti o si ṣẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò, inu rẹ̀, a si wú, itan rẹ̀ a si rà: obinrin na a si di ẹni egún lãrin awọn enia rẹ̀. 28 Bi obinrin na kò ba si ṣe ẹni ibàjẹ́, ṣugbọn ti o mọ́; njẹ yio yege, yio si lóyun. 29 Eyi li ofin owú, nigbati obinrin kan ba yapa, labẹ ọkọ rẹ̀, ti o si di ẹni ibàjẹ́; 30 Tabi nigbati ẹmi owú ba dé si ọkọ kan, ti o ba si njowú obinrin rẹ̀; nigbana yio mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki alufa ki o si ṣe gbogbo ofin yi si i. 31 Nigbana li ọkunrin na yio bọ́ kuro ninu aiṣedede, obinrin na yio si rù aiṣedede ara rẹ̀.

Numeri 6

Òfin fún Àwọn Nasiri

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba yà ara wọn sapakan lati ṣe ileri ti Nasiri, lati yà ara wọn si OLUWA: 3 Ki o yà ara rẹ̀ kuro ninu ọti-waini tabi ọti lile; ki o má si ṣe mu ọti-waini kikan, tabi ọti lile ti o kan, ki o má si ṣe mu ọti eso-àjara kan, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ eso-àjara tutù tabi gbigbẹ. 4 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ni ki o gbọdọ jẹ ohun kan ti a fi eso-àjara ṣe, lati kóro rẹ̀ titi dé ẽpo rẹ̀. 5 Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba. 6 Ni gbogbo ọjọ́ ti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, on kò gbọdọ sunmọ okú. 7 On kò gbọdọ sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀, nitori arakunrin rẹ̀, tabi nitori arabinrin rẹ̀, nigbati nwọn ba kú: nitoripe ìyasapakan Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀. 8 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA. 9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a. 10 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: 11 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na. 12 Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́. 13 Eyi si li ofin ti Nasiri, nigbati ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ba pé: ki a si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: 14 On o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ sisun, ati abo ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùkun fun ẹbọ alafia. 15 Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn. 16 Ki alufa ki o mú wọn wá siwaju OLUWA, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ati ẹbọ sisun rẹ̀: 17 Ki o si ru àgbo na li ẹbọ alafia si OLUWA, pẹlu agbọ̀n àkara alaiwu: ki alufa pẹlu ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 18 Ki Nasiri na ki o fá ori ìyasapakan rẹ̀ li ẹnu-ọ̀na agọ́ àjọ, ki o si mú irun ori ìyasapakan rẹ̀ ki o si fi i sinu iná ti mbẹ labẹ ẹbọ alafia na. 19 Ki alufa ki o si mú apá bibọ̀ àgbo na, ati àkara adidùn kan alaiwu kuro ninu agbọ̀n na, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan alaiwu, ki o si fi wọn lé ọwọ́ Nasiri na, lẹhin ìgba ti a fá irun ori ìyasapakan rẹ̀ tán: 20 Ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: mimọ́ li eyi fun alufa na, pẹlu àiya fifì, ati itan agbesọsoke: lẹhin na Nasiri na le ma mu ọti-waini. 21 Eyi li ofin ti Nasiri ti o ṣe ileri, ati ti ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA fun ìyasapakan rẹ̀ li àika eyiti ọwọ́ on le tẹ̀: gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, bẹ̃ni ki o ṣe nipa ofin ìyasapakan rẹ̀.

Ibukun Àlùfáà

22 OLUWA si sọ fun Mose pe, 23 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe, 24 Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́: 25 Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ: 26 Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia. 27 Bayi ni nwọn o fi orukọ mi sara awọn ọmọ Israeli; emi o si busi i fun wọn.

Numeri 7

Ẹbọ Àwọn Olórí

1 OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́; 2 Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá: 3 Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ. 4 OLUWA si sọ fun Mose pe, 5 Gbà a lọwọ wọn, ki nwọn ki o le jẹ́ ati fi ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ; ki iwọ ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀. 6 Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi. 7 Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn: 8 Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa. 9 Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù. 10 Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na. 11 OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ. 12 Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda. 13 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 14 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 15 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 16 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 17 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Naṣoni ọmọ Amminadabu. 18 Li ọjọ́ keji ni Netaneeli ọmọ Suari, olori ti Issakari mú ọrẹ wá: 19 On múwa fun ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ: 20 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 21 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 22 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 23 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Netaneeli ọmọ Suari. 24 Li ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olori awọn ọmọ Sebuluni: 25 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 26 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 27 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 28 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 29 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Eliabu ọmọ Heloni. 30 Li ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olori awọn ọmọ Reubeni; 31 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; 32 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 33 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 34 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 35 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 36 Li ọjọ́ karun Ṣelumieli ọmọ Suriṣuddai, olori awọn ọmọ Simeoni: 37 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; 38 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 39 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 40 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 41 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Ṣelumieli ọmọ Ṣuriṣaddai. 42 Li ọjọ́ kẹfa Eliasafu ọmọ Deueli, olori awọn ọmọ Gadi: 43 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; 44 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 45 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 46 Akọ ewure kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 47 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliasafu ọmọ Deueli. 48 Li ọjọ́ keje Eliṣama ọmọ Ammihudu, olori awọn ọmọ Efraimu: 49 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 50 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 51 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 52 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 53 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliṣama ọmọ Ammihudu. 54 Li ọjọ́ kẹjọ Gamalieli ọmọ Pedasuri, olori awọn ọmọ Manasse: 55 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 56 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 57 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 58 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 59 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Gamalieli ọmọ Pedasuri. 60 Li ọjọ́ kẹsan Abidani ọmọ Gideoni, olori awọn ọmọ Benjamini: 61 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 62 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 63 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 64 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 65 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Abidani ọmọ Gideoni. 66 Li ọjọ́ kẹwá ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olori awọn ọmọ Dani: 67 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ: 68 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 69 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 70 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 71 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 72 Li ọjọ́kọkanla Pagieli ọmọ Okrani, olori awọn ọmọ Aṣeri: 73 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 74 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 75 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 76 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 77 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Pagieli ọmọ Okrani. 78 Li ọjọ́ kejila Ahira ọmọ Enani, olori awọn ọmọ Naftali: 79 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; 80 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; 81 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; 82 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; 83 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahira ọmọ Enani. 84 Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, li ọjọ́ ti a ta oróro si i, lati ọwọ́ awọn olori Israeli wá: awopọkọ fadakà mejila, awokòto fadakà mejila, ṣibi wurà mejila: 85 Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; 86 Ṣibi wurà jẹ́ mejila, nwọn kún fun turari, ṣibi kọkan jẹ́ ṣekeli mẹwa, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; gbogbo wurà agọ́ na jẹ́ ọgọfa ṣekeli. 87 Gbogbo akọmalu fun ẹbọ sisun jẹ́ ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo mejila, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan mejila, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn: ati akọ ewurẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, mejila. 88 Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i. 89 Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.

Numeri 8

Ìgbékalẹ̀ Fìtílà

1 OLUWA si sọ fun Mose pẹ, 2 Sọ fun Aaroni, ki o si wi fun u pe, Nigbati iwọ ba tàn fitila, ki fitila mejeje na ki o ma tàn imọlẹ lori ọpá-fitila. 3 Aaroni si ṣe bẹ̃; o tàn fitila wọnni lori ọpá-fitila na, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 4 Iṣẹ ọpá-fitila na yi si jẹ̀ ti wurà lilù; titi dé isalẹ rẹ̀, titi dé itanna rẹ̀, o jẹ́ iṣẹ lulù: gẹgẹ bi apẹrẹ ti OLUWA fihàn Mose, bẹ̃li o ṣe ọpá-fitila na.

Ìwẹ̀nùmọ́ ati Ìyàsímímọ́ Àwọn Ọmọ Lefi

5 OLUWA si sọ fun Mose pe, 6 Yọ awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki o si wẹ̀ wọn mọ́. 7 Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́. 8 Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 9 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si pe gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli jọ pọ̀: 10 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA: ki awọn ọmọ Israeli ki o si fi ọwọ́ wọn lé awọn ọmọ Lefi. 11 Ki Aaroni ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, bi ọrẹ fifì lati ọdọ awọn ọmọ Israeli wá, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ-ìsin OLUWA. 12 Ki awọn ọmọ Lefi ki o si fi ọwọ́ wọn lé ori ẹgbọrọ akọmalu wọnni: ki iwọ ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun si OLUWA, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Lefi. 13 Ki iwọ ki o si mu awọn ọmọ Lefi duro niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì fun OLUWA. 14 Bẹ̃ni ki iwọ ki o yà awọn ọmọ Lefi sọ̀tọ kuro lãrin awọn ọmọ Israeli: awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi. 15 Lẹhin eyinì li awọn ọmọ Lefi yio ma wọ̀ inu ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si wẹ̀ wọn mọ́, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì. 16 Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi. 17 Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia ati ti ẹran: li ọjọ́ ti mo kọlù gbogbo akọ̀bi ni ilẹ Egipti ni mo ti yà wọn simimọ́ fun ara mi. 18 Emi si ti gbà awọn ọmọ Lefi dipò gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli. 19 Emi si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọrẹ lati inu awọn ọmọ Israeli wá, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Israeli ninu agọ́ ajọ, ati lati ma ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli: ki àrun má ba sí ninu awọn ọmọ Israeli, nigbati awọn ọmọ Israeli ba sunmọ ibi-mimọ́. 20 Bayi ni Mose, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ṣe si awọn ọmọ Lefi: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe si wọn. 21 Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́. 22 Lẹhin eyinì ni awọn ọmọ Lefi si wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀: bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃ni nwọn ṣe si wọn. 23 OLUWA si sọ fun Mose pe, 24 Eyi ni ti awọn ọmọ Lefi: lati ẹni ọdún mẹdọgbọ̀n lọ ati jù bẹ̃ lọ ni ki nwọn ki o ma wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ. 25 Ati lati ẹni ãdọta ọdún ni ki nwọn ki o ṣiwọ iṣẹ-ìsin, ki nwọn ki o má si ṣe sìn mọ́; 26 Bikoṣepe ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ pẹlu awọn arakunrin wọn ninu agọ́ ajọ, lati ma ṣe itọju, ki nwọn ki o má si ṣe iṣẹ-ìsin mọ́. Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si awọn ọmọ Lefi niti itọju wọn.

Numeri 9

Àjọ Ìrékọjá Keji

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe, 2 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ li akokò rẹ̀. 3 Li ọjọ́ kẹrinla oṣù yi, li aṣalẹ, ni ki ẹnyin ki o ma ṣe e li akokò rẹ̀: gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀ gbogbo, ati gẹgẹ bi ìlana rẹ̀ gbogbo, ni ki ẹnyin ki o pa a mọ́. 4 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́: 5 Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe. 6 Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na: 7 Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli? 8 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin. 9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA. 11 Li ọjọ́ kẹrinla oṣù keji li aṣalẹ ni ki nwọn ki o pa a mọ́; ki nwọn si fi àkara alaiwu jẹ ẹ ati ewebẹ kikorò: 12 Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e. 13 Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 14 Bi alejò kan ba si nṣe atipo lọdọ nyin, ti o si nfẹ́ pa irekọja mọ́ fun OLUWA; gẹgẹ bi ìlana irekọja, ati gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀, ni ki o ṣe bẹ̃: ìlana kan ni ki ẹnyin ki o ní, ati fun alejò, ati fun ibilẹ.

Ọ̀wọ̀n Iná

15 Ati li ọjọ́ ti a gbé agọ́ ró awọsanma si bò agọ́ na, eyinì ni, agọ́ ẹrí: ati li alẹ o si hàn lori agọ́ na bi iná, titi o fi di owurọ̀. 16 Bẹ̃li o si ri nigbagbogbo: awọsanma bò o, ati oye iná li oru. 17 Nigbati awọsanma ba ká soke kuro lori agọ́ na, lẹhin na awọn ọmọ Israeli a si ṣí: nibiti awọsanma ba si duro, nibẹ̀ li awọn ọmọ Israeli idó si. 18 Nipa aṣẹ OLUWA awọn ọmọ Israeli a ṣí, nipa aṣẹ OLUWA nwọn a si dó: ni gbogbo ọjọ́ ti awọsanma ba simi lori agọ́ na, nwọn a dó. 19 Nigbati awọsanma ba si pẹ li ọjọ́ pupọ̀ lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a si ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, nwọn ki si iṣi. 20 Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí. 21 Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí. 22 Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí. 23 Nipa aṣẹ OLUWA nwọn a dó, ati nipa aṣẹ OLUWA nwọn a ṣí: nwọn a ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.

Numeri 10

Àwọn Fèrè Fadaka

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó. 3 Nigbati nwọn ba fun wọn, ki gbogbo ijọ ki o pé sọdọ rẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 4 Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ. 5 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju. 6 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn. 7 Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri. 8 Awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ni ki o si fun ipè na; ki nwọn ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin ni iran-iran nyin. 9 Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin. 10 Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣí Àgọ́ Wọn

11 O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí. 12 Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani. 13 Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. 14 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu. 15 Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari si ni Netaneli ọmọ Suari. 16 Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni. 17 A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí. 18 Ọpágun ibudó Reubeni si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuri ọmọ Ṣedeuri si li olori ogun rẹ̀. 19 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai 20 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli. 21 Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn. 22 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Efraimu si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu si li olori ogun rẹ̀. 23 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse ni Gamalieli ọmọ Pedasuri. 24 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. 25 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Dani, ti o kẹhin gbogbo ibudó, si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 26 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okrani. 27 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali ni Ahira ọmọ Enani. 28 Bayi ni ìrin awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ogun wọn; nwọn si ṣí. 29 Mose si wi fun Hobabu, ọmọ Ragueli ara Midiani, ana Mose pe, Awa nṣí lọ si ibi ti OLUWA ti wi pe, Emi o fi i fun nyin: wá ba wa lọ, awa o ṣe ọ li ore: nitoripe OLUWA sọ̀rọ rere nipa Israeli. 30 On si wi fun u pe, Emi ki yio lọ; ṣugbọn emi o pada lọ si ilẹ mi, ati sọdọ ará mi. 31 O si wipe, Máṣe fi wa silẹ, emi bẹ̀ ọ; iwọ sà mọ̀ pe ni ijù li awa dó si, iwọ o si ma ṣe oju fun wa. 32 Yio si ṣe, bi iwọ ba bá wa lọ, yio si ṣe, pe, orekore ti OLUWA ba ṣe fun wa, on na li awa o ṣe fun ọ.

Àwọn Eniyan náà Tẹ̀síwájú

33 Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn. 34 Awọsanma OLUWA mbẹ lori wọn li ọsán, nigbati nwọn ba ṣí kuro ninu ibudó. 35 O si ṣe, nigbati apoti ẹrí ba ṣí siwaju, Mose a si wipe, Dide, OLUWA, ki a si tú awọn ọtá rẹ ká; ki awọn ti o korira rẹ ki o si salọ kuro niwaju rẹ. 36 Nigbati o ba si simi, on a wipe, Pada, OLUWA, sọdọ ẹgbẹgbarun awọn enia Israeli.

Numeri 11

Ibi tí Wọn sọ ní Tabera

1 AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na. 2 Awọn enia na si kigbe tọ̀ Mose lọ; nigbati Mose si gbadura si OLUWA, iná na si rẹlẹ. 3 O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Tabera: nitoriti iná OLUWA jó lãrin wọn.

Mose Yan Aadọrin Olórí

4 Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? 5 Awa ranti ẹja, ti awa ti njẹ ni Egipti li ọfẹ; ati apálà, ati bàra, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko: 6 Ṣugbọn nisisiyi ọkàn wa gbẹ: kò sí ohun kan rára, bikọse manna yi niwaju wa. 7 Manna na si dabi irugbìn korianderi, àwọ rẹ̀ si dabi àwọ okuta-bedeliumu. 8 Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro. 9 Nigbati ìri ba si sẹ̀ si ibudó li oru, manna a bọ́ si i. 10 Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose. 11 Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi? 12 Iṣe emi li o lóyun gbogbo enia yi? iṣe emi li o bi wọn, ti iwọ fi wi fun mi pe, Ma gbé wọn lọ li õkanaiya rẹ, bi baba iti igbé ọmọ ọmú, si ilẹ ti iwọ ti bura fun awọn baba wọn. 13 Nibo li emi o gbé ti mú ẹran wá fi fun gbogbo enia yi? nitoriti nwọn nsọkun si mi wipe, Fun wa li ẹran, ki awa ki o jẹ. 14 Emi nikan kò le rù gbogbo awọn enia yi, nitoriti nwọn wuwo jù fun mi. 15 Ati bi bayi ni iwọ o ṣe si mi, emi bẹ̀ ọ, pa mi kánkan, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ; má si ṣe jẹ ki emi ri òṣi mi. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, Pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba Israeli jọ sọdọ mi, ẹniti iwọ mọ̀ pe, nwọn ṣe àgba awọn enia, ati olori wọn; ki o si mú wọn wá si agọ́ ajọ, ki nwọn ki o si duro nibẹ̀ pẹlu rẹ. 17 Emi o si sọkalẹ wá, emi o si bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀: emi o si mú ninu ẹmi ti mbẹ lara rẹ, emi o si fi i sara wọn; nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù awọn enia na, ki iwọ ki o máṣe nikan rù u. 18 Ki iwọ ki o si wi fun awọn enia na pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ dè ọla, ẹnyin o si jẹ ẹran: nitoriti ẹnyin sọkun li etí OLUWA, wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? o sá dara fun wa ni Egipti: nitorina ni OLUWA yio ṣe fun nyin li ẹran, ẹnyin o si jẹ. 19 Ẹ ki o jẹ ni ijọ́ kan, tabi ni ijọ́ meji, tabi ni ijọ́ marun, bẹ̃ni ki iṣe ijọ́ mẹwa, tabi ogún ọjọ́; 20 Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá? 21 Mose si wipe, Awọn enia na, lãrin awọn ẹniti emi wà, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀; iwọ si wipe, Emi o fun wọn li ẹran, ki nwọn ki o le ma jẹ li oṣù kan tọ̀tọ. 22 Agbo-ẹran tabi ọwọ́-ẹran ni ki a pa fun wọn, lati tó fun wọn ni? tabi gbogbo ẹja okun li a o kójọ fun wọn lati tó fun wọn? 23 OLUWA si sọ fun Mose pe, Ọwọ́ OLUWA ha kúru bi? iwọ o ri i nisisiyi bi ọ̀rọ mi yio ṣẹ si ọ, tabi bi ki yio ṣẹ. 24 Mose si jade lọ, o si sọ ọ̀rọ OLUWA fun awọn enia: o si pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba enia jọ, o si mu wọn duro yi agọ́ ká. 25 OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́. 26 Ṣugbọn o kù meji ninu awọn ọkunrin na ni ibudó, orukọ ekini a ma jẹ́ Eldadi, orukọ ekeji Medadi: ẹmi na si bà lé wọn; nwọn si mbẹ ninu awọn ti a kà, ṣugbọn nwọn kò jade lọ si agọ́: nwọn si nsọtẹlẹ ni ibudó. 27 Ọmọkunrin kan si súre, o si sọ fun Mose, o si wipe, Eldadi ati Medadi nsọtẹlẹ ni ibudó. 28 Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọkan ninu awọn ọmọkunrin rẹ̀ dahùn, o si wipe, Mose oluwa mi, dá wọn lẹkun. 29 Mose si wi fun u pe, Iwọ njowú nitori mi? gbogbo enia OLUWA iba le jẹ́ wolĩ, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ̀ si wọn lara! 30 Mose si lọ si ibudó, on ati awọn àgba Israeli.

OLUWA Darí Àwọn Àparò Sọ́dọ̀ Wọn

31 Afẹfẹ kan si ti ọdọ OLUWA jade lọ, o si mú aparò lati okun wá, o si dà wọn si ibudó, bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ihin, ati bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ọhún yi ibudó ká, ni ìwọn igbọnwọ meji lori ilẹ. 32 Awọn enia si duro ni gbogbo ọjọ́ na, ati ni gbogbo oru na, ati ni gbogbo ọjọ́ keji, nwọn si nkó aparò: ẹniti o kó kére, kó òṣuwọn homeri mẹwa: nwọn si sá wọn silẹ fun ara wọn yi ibudó ká. 33 Nigbati ẹran na si mbẹ lãrin ehín wọn, ki nwọn ki o tó jẹ ẹ, ibinu OLUWA si rú si awọn enia na, OLUWA si fi àrun nla gidigidi kọlù awọn enia na. 34 A si pè orukọ ibẹ̀ na ni Kibrotu-hattaafa: nitoripe nibẹ̀ ni nwọn gbé sinku awọn enia ti o ṣe ifẹkufẹ. 35 Awọn enia na si dide ìrin wọn lati Kibrotu-hattaafa lọ si Haserotu; nwọn si dó si Haserotu.

Numeri 12

Ìjìyà Miriamu

1 A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo. 2 Nwọn si wipe, Nipa Mose nikan ni OLUWA ha sọ̀rọ bi? kò ha ti ipa wa sọ̀rọ pẹlu? OLUWA si gbọ́ ọ. 3 Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ. 4 OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade. 5 OLUWA si sọkalẹ wá ninu ọwọ̀n awọsanma, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na, o si pè Aaroni ati Miriamu: awọn mejeji si jade wá. 6 O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá. 7 Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi. 8 On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi? 9 Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ. 10 Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ. 11 Aaroni si wi fun Mose pe, Yẽ, oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, máṣe kà ẹ̀ṣẹ na si wa lọrùn, eyiti awa fi wère ṣe, ati eyiti awa ti dẹ̀ṣẹ. 12 Emi bẹ̀ ọ máṣe jẹ ki o dabi ẹniti o kú, ẹniti àbọ ara rẹ̀ run tán nigbati o ti inu iya rẹ̀ jade. 13 Mose si kigbe pè OLUWA, wipe, Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, mu u lara dá nisisiyi. 14 OLUWA si wi fun Mose pe, Bi baba rẹ̀, tilẹ tu itọ si i li oju, njẹ oju ki ba tì i ni ijọ́ meje? Ki a sé e mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje, lẹhin eyinì ki a gbà a sinu rẹ̀. 15 A si sé Miriamu mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje: awọn enia kò si ṣí titi a fi gbà Miriamu pada. 16 Lẹhin eyinì li awọn enia si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si ijù Parani.

Numeri 13

Mose Rán Amí lọ sí Ilẹ̀ Kenaani

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn. 3 Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli. 4 Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru. 5 Ninu ẹ̀ya Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori. 6 Ninu ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne. 7 Ninu ẹ̀ya Issakari, Igali ọmọ Josefu. 8 Ninu ẹ̀ya Efraimu, Oṣea ọmọ Nuni. 9 Ninu ẹ̀ya Benjamini, Palti ọmọ Rafu. 10 Ninu ẹ̀ya Sebuluni, Gaddieli ọmọ Sodi. 11 Ninu ẹ̀ya Josefu, eyinì ni, ninu ẹ̀ya Manasse, Gadi ọmọ Susi. 12 Ninu ẹ̀ya Dani, Ammieli ọmọ Gemalli. 13 Ninu ẹ̀ya Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli. 14 Ninu ẹ̀ya Naftali, Nabi ọmọ Fofsi. 15 Ninu ẹ̀ya Gaddi, Geueli ọmọ Maki. 16 Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin na, ti Mose rán lati lọ ṣe amí ilẹ na. Mose si sọ Oṣea ọmọ Nuni ni Joṣua. 17 Mose si rán wọn lọ ṣe amí ilẹ Kenaani, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà ọ̀na ìha gusù yi, ki ẹ sì lọ sori òke nì. 18 Ki ẹnyin si wò ilẹ na, bi o ti ri; ati awọn enia ti ngbé inu rẹ̀, bi nwọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni nwọn, tabi pupọ̀; 19 Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi; 20 Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara. 21 Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati. 22 Nwọn si ti ìha gusù gòke lọ, nwọn si dé Hebroni; nibiti Ahimani, Ṣeṣai, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki gbé wà. (A ti tẹ̀ Hebroni dò li ọdún meje ṣaju Soani ni Egipti.) 23 Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá. 24 Nwọn si sọ ibẹ̀ na ni odò Eṣkolu, nitori ìdi-eso ti awọn ọmọ Israeli rẹ́ lati ibẹ̀ wá. 25 Nwọn si pada ni rirìn ilẹ na wò lẹhin ogoji ọjọ́. 26 Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn. 27 Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀. 28 Ṣugbọn alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀. 29 Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani. 30 Kalebu si pa awọn enia lẹnu mọ́ niwaju Mose, o si wipe, Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹ̃kan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ́ ẹ. 31 Ṣugbọn awọn ọkunrin ti o bá a gòke lọ wipe, Awa kò le gòke tọ̀ awọn enia na lọ; nitoriti nwọn lagbara jù wa lọ. 32 Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ. 33 Ati nibẹ̀ li awa gbé ri awọn omirán, awọn ọmọ Anaki ti o ti inu awọn omirán wá: awa si dabi ẹlẹnga li oju ara wa, bẹ̃li awa si ri li oju wọn.

Numeri 14

Àwọn Eniyan náà Kùn

1 GBOGBO ijọ si gbé ohùn wọn soke, nwọn si ke: awọn enia na si sọkun li oru na. 2 Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi! 3 Nitori kini OLUWA ṣe mú wa wá si ilẹ yi, lati ti ipa idà ṣubu? Awọn aya wa, ati awọn ọmọ wa yio di ijẹ: kò ha san fun wa ki a pada lọ si Egipti? 4 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẹ jẹ ki a yàn olori, ki a si pada lọ si Egipti. 5 Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli. 6 Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya: 7 Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi. 8 Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 9 Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. 10 Gbogbo ijọ si wipe ki a sọ wọn li okuta. Ṣugbọn ogo OLUWA hàn ninu agọ́ ajọ niwaju gbogbo awọn ọmọ Israeli.

Mose Gbadura fún Àwọn Eniyan náà

11 OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn? 12 Emi o fi ajakalẹ-àrun kọlù wọn, emi o si gbà ogún wọn lọwọ wọn, emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla, ati alagbara jù wọn lọ. 13 Mose si wi fun OLUWA pe, Ṣugbọn awọn ara Egipti yio gbọ́; nitoripe nipa agbara rẹ ni iwọ fi mú awọn enia yi jade lati inu wọn wá; 14 Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru. 15 Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe, 16 Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù. 17 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe, 18 Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin. 19 Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi. 20 OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: 21 Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA; 22 Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; 23 Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i: 24 Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i. 25 Njẹ awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani ngbé afonifoji: li ọla ẹ pada, ki ẹ si ṣi lọ si aginjù nipa ọ̀na Okun Pupa.

OLUWA Jẹ Àwọn Eniyan náà Níyà Nítorí pé wọ́n Kùn

26 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 27 Emi o ti mu sũru pẹ to fun ijọ enia buburu yi ti nkùn si mi? Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli, ti nwọn kùn si mi. 28 Wi fun wọn pe, OLUWA wipe, Bi mo ti wà nitõtọ, bi ẹnyin ti sọ li etí mi, bẹ̃li emi o ṣe si nyin: 29 Okú nyin yio ṣubu li aginjù yi; ati gbogbo awọn ti a kà ninu nyin, gẹgẹ bi iye gbogbo nyin, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jú bẹ̃ lọ, ti ẹ kùn si mi, 30 Ẹnyin ki yio dé inu ilẹ na, ti mo ti bura lati mu nyin gbé inu rẹ̀, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni. 31 Ṣugbọn awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe yio di ijẹ, awọn li emi o muwọ̀ ọ, awọn ni yio si mọ̀ ilẹ na ti ẹnyin gàn. 32 Ṣugbọn ẹnyin, okú nyin yio ṣubu li aginjú yi. 33 Awọn ọmọ nyin yio si ma rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, nwọn o si ma rù ìwa-àgbere nyin, titi okú nyin yio fi ṣòfo tán li aginjù. 34 Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́. 35 Emi OLUWA ti sọ, Emi o ṣe e nitõtọ si gbogbo ijọ buburu yi, ti nwọn kójọ pọ̀ si mi: li aginjù yi ni nwọn o run, nibẹ̀ ni nwọn o si kú si. 36 Ati awọn ọkunrin na ti Mose rán lọ lati rìn ilẹ na wò, ti nwọn pada, ti nwọn si mu gbogbo ijọ kùn si i, ni mimú ìhin buburu ilẹ na wá, 37 Ani awọn ọkunrin na ti o mú ìhin buburu ilẹ na wá, nwọn ti ipa àrun kú niwaju OLUWA. 38 Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ati Kalebu ọmọ Jefunne, ninu awọn ọkunrin na ti o rìn ilẹ na lọ, wà lãye.

Ìgbà Kinni Tí Wọ́n Gbìyànjú àtigba Ilẹ̀ náà

39 Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi. 40 Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀. 41 Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin. 42 Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin. 43 Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin. 44 Ṣugbọn nwọn fi igberaga gòke lọ sori òke na: ṣugbọn apoti ẹrí OLUWA, ati Mose, kò jade kuro ni ibudò. 45 Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.

Numeri 15

Àwọn Òfin nípa Ìrúbọ

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ibujoko nyin, ti mo fi fun nyin, 3 Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran: 4 Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò: 5 Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan. 6 Tabi fun àgbo kan, ki iwọ ki o pèse ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun pẹlu idamẹta òṣuwọn hini oróro: 7 Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA. 8 Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA: 9 Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò. 10 Ki iwọ ki o si múwa fun ẹbọ ohunmimu àbọ òṣuwọn hini ọti-waini, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 11 Bayi ni ki a ṣe niti akọmalu kan, tabi niti àgbo kan, tabi niti akọ ọdọ-agutan kan, tabi niti ọmọ-ewurẹ kan. 12 Gẹgẹ bi iye ti ẹnyin o pèse, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe si olukuluku gẹgẹ bi iye wọn. 13 Gbogbo ibilẹ ni ki o ma ṣe nkan wọnyi bayi, nigbati nwọn ba nru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA. 14 Ati bi alejò kan ba nṣe atipo lọdọ nyin, tabi ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin ni iran nyin, ti o si nfẹ́ ru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; bi ẹnyin ti ṣe, bẹ̃ni ki on ki o ṣe. 15 Ìlana kan ni ki o wà fun ẹnyin ijọ enia, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin, ìlana titilai, ni iran-iran nyin: bi ẹnyin ti ri, bẹ̃ni ki alejò ki o si ri niwaju OLUWA. 16 Ofin kan ati ìlana kan ni ki o wà fun nyin, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin. 17 OLUWA si sọ fun Mose pe, 18 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ na nibiti emi nmú nyin lọ, 19 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba njẹ ninu onjẹ ilẹ na, ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA. 20 Ki ẹnyin ki o mú àkara atetekọṣu iyẹfun nyin wá fun ẹbọ igbesọsoke: bi ẹnyin ti ṣe ti ẹbọ igbesọsoke ilẹ ipakà, bẹ̃ni ki ẹnyin gbé e sọ. 21 Ninu atetekọ́ṣu iyẹfun nyin ni ki ẹnyin ki o fi fun OLUWA li ẹbọ igbesọsoke, ni iran-iran nyin. 22 Bi ẹnyin ba si ṣìṣe, ti ẹnyin kò si kiyesi gbogbo ofin wọnyi ti OLUWA ti sọ fun Mose, 23 Ani gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun nyin lati ọwọ́ Mose wá, lati ọjọ́ na ti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati lati isisiyi lọ, ni iran-iran nyin; 24 Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 25 Ki alufa ki o si ṣètutu fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, a o si darijì wọn; nitoripe aimọ̀ ni, nwọn si ti mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn niwaju OLUWA, nitori aimọ̀ wọn: 26 A o si darijì gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ati alejò ti iṣe atipo lọdọ wọn; nitoripe gbogbo enia wà li aimọ̀. 27 Bi ọkàn kan ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, nigbana ni ki o mú abo-ewurẹ ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 28 Ki alufa ki o ṣètutu fun ọkàn na ti o ṣẹ̀, nigbati o ba ṣẹ̀ li aimọ̀ niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun u; a o si darijì i. 29 Ofin kan ni ki ẹnyin ki o ní fun ẹniti o ṣẹ̀ ni aimọ̀, ati fun ẹniti a bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn. 30 Ṣugbọn ọkàn na ti o ba fi ikugbu ṣe ohun kan, iba ṣe ibilẹ tabi alejò, o sọ̀rọbuburu si OLUWA; ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 31 Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. 32 Nigbati awọn ọmọ Israeli wà li aginjù, nwọn ri ọkunrin kan ti nṣẹ́ igi li ọjọ́-isimi. 33 Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ. 34 Nwọn si há a mọ́ ile-ìde, nitoriti a kò ti isọ bi a o ti ṣe e. 35 OLUWA si sọ fun Mose pe, Pipa li a o pa ọkunrin na: gbogbo ijọ ni yio sọ ọ li okuta pa lẹhin ibudó. 36 Gbogbo ijọ si mú u wá sẹhin ibudó, nwọn si sọ ọ li okuta, on si kú; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Òfin nípa Kókó Etí Aṣọ

37 OLUWA si sọ fun Mose pe, 38 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na: 39 Yio si ma ṣe bi wajawaja fun nyin, ki ẹnyin ki o le ma wò o, ki ẹ si ma ranti gbogbo ofin OLUWA, ki ẹ si ma ṣe wọn: ki ẹnyin ki o má si ṣe tẹle ìro ọkàn nyin ati oju ara nyin, ti ẹnyin ti ima ṣe àgbere tọ̀ lẹhin: 40 Ki ẹnyin ki o le ma ranti, ki ẹ si ma ṣe ofin mi gbogbo, ki ẹnyin ki o le jẹ́ mimọ́ si Ọlọrun nyin. 41 Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.

Numeri 16

Ọ̀tẹ̀ tí Kora, Datani ati Abiramu Dì

1 NJẸ Kora, ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ati Datani on Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ati On, ọmọ Peleti, awọn ọmọ Reubeni, dìmọ: 2 Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí: 3 Nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, nwọn si wi fun wọn pe, O tó gẹ, nitoripe gbogbo ijọ li o jẹ́ mimọ́, olukuluku wọn, OLUWA si mbẹ lãrin wọn: nitori kili ẹnyin ha ṣe ngbé ara nyin ga jù ijọ OLUWA lọ? 4 Nigbati Mose gbọ́, o doju rẹ̀ bolẹ: 5 O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀. 6 Ẹ ṣe eyi; Ẹ mú awo-turari, Kora, ati gbogbo ẹgbẹ rẹ̀; 7 Ki ẹ si fi iná sinu wọn, ki ẹ si fi turari sinu wọn niwaju OLUWA li ọla: yio si ṣe, ọkunrin ti OLUWA ba yàn, on ni ẹni mimọ́: o tó gẹ, ẹnyin ọmọ Lefi. 8 Mose si wi fun Kora pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹnyin ọmọ Lefi, ẹ gbọ́: 9 Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn; 10 O si mú iwọ sunmọ ọdọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ gbogbo, awọn ọmọ Lefi pẹlu rẹ; ẹnyin si nwá iṣẹ-alufa pẹlu? 11 Nitorina, iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ kójọ pọ̀ si OLUWA: ati kini Aaroni, ti ẹnyin nkùn si i? 12 Mose si ranṣẹ pè Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu: nwọn si wipe, Awa ki yio gòke wá: 13 Ohun kekere ha ni ti iwọ mú wa gòke lati ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin wá, lati pa wa li aginjù, ti iwọ fi ara rẹ jẹ́ alade lori wa patapata? 14 Pẹlupẹlu iwọ kò ti imú wa dé ilẹ kan ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bẹ̃ni iwọ kò fun wa ni iní ilẹ ati ọgba-àjara: iwọ o yọ oju awọn ọkunrin wọnyi bi? awa ki yio gòke wá. 15 Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara. 16 Mose wi fun Kora pe, Ki iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ ki o wá siwaju OLUWA, iwọ, ati awọn, ati Aaroni li ọla: 17 Ki olukuluku wọn ki o mú awo-turari rẹ̀, ki ẹ si fi turari sinu wọn, ki olukuluku nyin ki o mú awo-turari rẹ̀ wá siwaju OLUWA, ãdọtalerugba awo-turari; iwọ pẹlu ati Aaroni, olukuluku awo-turari rẹ̀. 18 Olukuluku wọn si mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari lé ori wọn, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, pẹlu Mose ati Aaroni. 19 Kora si kó gbogbo ijọ enia jọ si wọn si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ogo OLUWA si hàn si gbogbo ijọ enia na. 20 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, 21 Ẹ yà ara nyin kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣéju kan. 22 Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ? 23 OLUWA si sọ fun Mose pe, 24 Sọ fun ijọ pe, Ẹ gòke wá kuro ni sakani agọ́ Kora, Datani, ati Abiramu. 25 Mose si dide, o si tọ̀ Datani ati Abiramu lọ; awọn àgba Israeli si tẹle e. 26 O si sọ fun ijọ pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ kuro ni ibi agọ́ awọn ọkunrin buburu yi, ẹ má si ṣe fọwọkàn ohun kan ti iṣe ti wọn, ki ẹ má ba run ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn. 27 Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ. 28 Mose si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe OLUWA li o rán mi lati ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi; ati pe emi kò ṣe wọn lati inu ara mi wá. 29 Bi awọn ọkunrin wọnyi ba kú bi gbogbo enia ti ikú, tabi bi a ba si bẹ̀ wọn wò bi ãti ibẹ̀ gbogbo enia wò; njẹ OLUWA ki o rán mi. 30 Ṣugbọn bi OLUWA ba ṣe ohun titun, ti ilẹ ba si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, pẹlu ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, ti nwọn si sọkalẹ lọ si ipò-okú lãye; nigbana ẹnyin o mọ̀ pe awọn ọkunrin wọnyi ti gàn OLUWA. 31 O si ṣe, bi o ti pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni sisọ, ni ilẹ là pẹrẹ nisalẹ wọn: 32 Ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si gbe wọn mì, ati awọn ara ile wọn, ati gbogbo awọn enia ti iṣe ti Kora, ati gbogbo ẹrù wọn. 33 Awọn, ati ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, sọkalẹ lọ lãye si ipò-okú, ilẹ si pa ẹnu dé mọ́ wọn, nwọn si run kuro ninu ijọ. 34 Gbogbo enia Israeli ti o yi wọn ká si salọ nitori igbe wọn: nitoriti nwọn wipe, Ki ilẹ ki o má ba gbe wa mì pẹlu. 35 Iná si jade wá lati ọdọ OLUWA, o si run awọn ãdọtalerugba ọkunrin nì ti nwọn mú turari wá.

Àwọn Àwo Turari

36 OLUWA si sọ fun Mose pe, 37 Sọ fun Eleasari ọmọ Aaroni alufa, pe ki o mú awo-turari wọnni kuro ninu ijóna, ki iwọ ki o si tu iná na ká sọhún; nitoripe nwọn jẹ́ mimọ́. 38 Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli. 39 Eleasari alufa si mú awo-turari idẹ wọnni, eyiti awọn ẹniti o jóna fi mú ẹbọ wá; a si rọ wọn li awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: 40 Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.

Aaroni Gba Àwọn Eniyan náà Là

41 Ṣugbọn ni ijọ́ keji gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli nkùn si Mose ati si Aaroni, wipe, Ẹnyin pa awọn enia OLUWA. 42 O si ṣe, nigbati ijọ pejọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, ti nwọn si wò ìha agọ́ ajọ: si kiyesi i, awọsanma bò o, ogo OLUWA si farahàn. 43 Mose ati Aaroni si wá siwaju agọ́ ajọ. 44 OLUWA si sọ fun Mose pe, 45 Ẹ lọ kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣẹju kan. Nwọn si doju wọn bolẹ. 46 Mose si wi fun Aaroni pe, Mú awo-turari kan, ki o si fi iná sinu rẹ̀ lati ori pẹpẹ nì wá, ki o si fi turari lé ori rẹ̀, ki o si yára lọ sọdọ ijọ, ki o si ṣètutu fun wọn: nitoriti ibinu jade lati ọdọ OLUWA lọ; iyọnu ti bẹ̀rẹ na. 47 Aaroni si mú awo-turari bi Mose ti fi aṣẹ fun u, o si sure lọ sãrin ijọ; si kiyesi i, iyọnu ti bẹ̀rẹ na lãrin awọn enia: o si fi turari sinu rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn enia na. 48 O si duro li agbedemeji okú ati alãye; iyọnu na si duro. 49 Awọn ti o kú ninu iyọnu na si jẹ́ ẹgba meje o le ẹ̃dẹgbẹrin, laìka awọn ti o kú niti ọ̀ran Kora. 50 Aaroni si pada tọ̀ Mose lọ si ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: iyọnu na si duro.

Numeri 17

Ọ̀pá Aaroni

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀. 3 Ki o si kọ orukọ Aaroni sara ọpá Lefi: nitoripe ọpá kan yio jẹ́ fun ori ile awọn baba wọn. 4 Ki o si fi wọn lelẹ ninu agọ́ ajọ, niwaju ẹrí, nibiti emi o gbé pade nyin. 5 Yio si ṣe, ọpá ẹniti emi o yàn yio ruwe: emi o si da kikùn awọn ọmọ Israeli duro kuro lọdọ mi, ti nwọn nkùn si nyin. 6 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn olori wọn si fun u li ọpá, ọpá kan fun olori kan, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, ani ọpá mejila: ọpá Aaroni si wà ninu ọpá wọn. 7 Mose si fi ọpá wọnni lelẹ niwaju OLUWA ninu agọ́ ẹrí. 8 O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi. 9 Mose si kó gbogbo ọpá na lati iwaju OLUWA jade tọ̀ gbogbo awọn ọmọ Israeli wá: nwọn si wò, olukuluku si mú ọpá tirẹ̀. 10 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú. 11 Mose si ṣe bẹ̃: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe. 12 Awọn ọmọ Israeli si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, awa kú, awa gbé, gbogbo wa gbé. 13 Ẹnikẹni ti o ba sunmọ agọ́ OLUWA yio kú: awa o ha fi kikú run bi?

Numeri 18

Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáàa ati Àwọn Ọmọ Lefi

1 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati ile baba rẹ pẹlu rẹ, ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ ibi-mimọ́: ati iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ iṣẹ-alufa nyin. 2 Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí. 3 Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ mọ́, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju gbogbo agọ́, kìki pe nwọn kò gbọdọ sunmọ ohun-èlo ibi-mimọ́ ati pẹpẹ, ki ati awọn, ati ẹnyin pẹlu ki o má ba kú. 4 Ki nwọn ki o si dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju agọ́ ajọ, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin agọ́: alejò kan kò sí gbọdọ sunmọ ọdọ nyin. 5 Ki ẹnyin ki o si ma ṣe itọju ibi-mimọ́, ati itọju pẹpẹ: ki ibinu ki o má ba sí mọ́ lori awọn ọmọ Israeli. 6 Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. 7 Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.

Ìpín Àwọn Àlùfáà

8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai. 9 Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ. 10 Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ. 11 Eyi si ni tirẹ; ẹbọ igbesọsoke ẹ̀bun wọn, pẹlu gbogbo ẹbọ fifì awọn ọmọ Israeli: emi ti fi wọn fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: gbogbo awọn ti o mọ́ ninu ile rẹ ni ki o jẹ ẹ. 12 Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun. 13 Akọ́so gbogbo ohun ti o wà ni ilẹ wọn, ti nwọn o mú fun OLUWA wá, tirẹ ni yio jẹ́; gbogbo ẹniti o mọ́ ni ile rẹ ni ki o jẹ ẹ. 14 Ohun ìyasọtọ gbogbo ni Israeli ni ki o jẹ́ tirẹ. 15 Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ. 16 Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera). 17 Ṣugbọn akọ́bi akọmalu, tabi akọbi agutan, tabi akọ́bi ewurẹ, ni iwọ kò gbọdọ ràsilẹ; mimọ́ ni nwọn: ẹ̀jẹ wọn ni ki iwọ ki o ta sori pẹpẹ, ki iwọ ki o si sun ọrá wọn li ẹbọ ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si OLUWA. 18 Ki ẹran wọn ki o si jẹ́ tirẹ, bi àiya fifì, ati bi itan ọtún, ni yio jẹ́ tirẹ. 19 Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ. 20 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli.

Ìpín Àwọn Ọmọ Lefi

21 Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. 22 Awọn ọmọ Israeli kò si gbọdọ sunmọ agọ́ ajọ, ki nwọn ki o má ba rù ẹ̀ṣẹ, ki nwọn má ba kú. 23 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní. 24 Nitori idamẹwa awọn ọmọ Israeli, ti nwọn múwa li ẹbọ igbesọsoke fun OLUWA, ni mo ti fi fun awọn ọmọ Lefi lati ní: nitorina ni mo ṣe wi fun wọn pe, Nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ Israeli.

Ìdámẹ́wàá Àwọn Ọmọ Lefi

25 OLUWA si sọ fun Mose pe, 26 Si sọ fun awọn ọmọ Lefi, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbà idamẹwa ti mo ti fi fun nyin ni ilẹiní nyin lọwọ awọn ọmọ Israeli, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke ninu rẹ̀ wá fun OLUWA, idamẹwa ninu idamẹwa na. 27 A o si kà ẹbọ igbesọsoke nyin yi si nyin, bi ẹnipe ọkà lati ilẹ ipakà wá, ati bi ọti lati ibi ifunti wá. 28 Bayi li ẹnyin pẹlu yio ma mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA ninu gbogbo idamẹwa nyin, ti ẹnyin ngbà lọwọ awọn ọmọ Israeli; ki ẹnyin ki o si mú ẹbọ igbesọsoke OLUWA ninu rẹ̀ tọ̀ Aaroni alufa wá. 29 Ninu gbogbo ẹ̀bun nyin ni ki ẹnyin ki o si mú gbogbo ẹbọ igbesọsoke OLUWA wá, ninu gbogbo eyiti o dara, ani eyiti a yàsimimọ́ ninu rẹ̀. 30 Nitorina ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke, nigbana ni ki a kà a fun awọn ọmọ Lefi bi ọkà ilẹ-ipakà, ati bi ibisi ibi-ifunti. 31 Ẹnyin o si jẹ ẹ ni ibi gbogbo, ati ẹnyin ati awọn ara ile nyin: nitoripe ère nyin ni fun iṣẹ-ìsin nyin ninu agọ́ ajọ. 32 Ẹnyin ki yio si rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ki ẹnyin ki o má ba kú.

Numeri 19

Eérú Mààlúù Pupa náà

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, 2 Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́: 3 Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀: 4 Ki Eleasari alufa, ki o fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n iwaju agọ́ ajọ ni ìgba meje. 5 Ki ẹnikan ki o si sun ẹgbọrọ abomalu na li oju rẹ̀; awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati ẹ̀jẹ rẹ̀, pẹlu igbẹ́ rẹ̀, ni ki o sun: 6 Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun. 7 Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 8 Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 9 Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. 10 Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.

Òfin Tí ó Jẹ Mọ́ Fífi Ara Kan òkú

11 Ẹniti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ki o jẹ́ alaimọ ni ijọ́ meje. 12 Ki oluwarẹ̀ ki o fi i wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje yio di mimọ́: ṣugbọn bi kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ ni ijọ́ kẹta, njẹ ni ijọ́ keje ki yio di mimọ́. 13 Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀, 14 Eyi li ofin na, nigbati enia kan ba kú ninu agọ́ kan: gbogbo ẹniti o wọ̀ inu agọ́ na, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu agọ́ na, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje. 15 Ati ohun-èlo gbogbo ti o ṣi silẹ, ti kò ní ideri lori rẹ̀, alaimọ́ ni. 16 Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje. 17 Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan: 18 Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú: 19 Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ. 20 Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on. 21 Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. 22 Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Numeri 20

Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ ní Kadeṣi

1 AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀. 2 Omi kò si sí fun ijọ: nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni. 3 Awọn enia si mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Awa iba kuku ti kú nigbati awọn arakunrin wa kú niwaju OLUWA! 4 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú ijọ OLUWA wá si aginjù yi, ki awa ati ẹran wá ki o kú nibẹ̀? 5 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu. 6 Mose ati Aaroni si lọ kuro niwaju ijọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, nwọn si doju wọn bolẹ: ogo OLUWA si hàn si wọn. 7 OLUWA si sọ fun Mose pe, 8 Mú ọpá nì, ki o si pe ijọ awọn enia jọ, iwọ, ati Aaroni arakunrin rẹ, ki ẹ sọ̀rọ si apata nì li oju wọn, yio si tú omi rẹ̀ jade; iwọ o si mú omi lati inu apata na jade fun wọn wá: iwọ o si fi fun ijọ ati fun ẹran wọn mu. 9 Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ. 10 Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi? 11 Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu. 12 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn. 13 Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.

Ọba Edomu kò Jẹ́ kí Àwọn Ọmọ Israẹli Kọjá

14 Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa: 15 Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa: 16 Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ: 17 Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ. 18 Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà. 19 Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja. 20 O si wipe, Iwọ ki yio là ilẹ kọja. Edomu si mú ọ̀pọ enia jade tọ̀ ọ wá pẹlu ọwọ́ agbara. 21 Bẹ̃li Edomu kọ̀ lati fi ọ̀na fun Israeli li àgbegbe rẹ̀: Israeli si ṣẹri kuro lọdọ rẹ̀.

Ikú Aaroni

22 Awọn ọmọ Israeli, ani gbogbo ijọ si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si wá si òke Hori. 23 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni li òke Hori li àgbegbe ilẹ Edomu wipe, 24 A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba. 25 Mú Aaroni ati Eleasari ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá si ori-òke Hori: 26 Ki o si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, ki o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀: a o si kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, yio si kú nibẹ̀. 27 Mose si ṣe bi OLUWA ti fun u li aṣẹ: nwọn si gòke lọ si ori òke Hori li oju gbogbo ijọ. 28 Mose si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀; Aaroni si kú nibẹ̀ li ori òke na: Mose ati Eleasari si sọkalẹ lati ori òke na wá. 29 Nigbati gbogbo ijọ ri pe Aaroni kú, nwọn ṣọfọ Aaroni li ọgbọ̀n ọjọ́, ani gbogbo ile Israeli.

Numeri 21

Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Kenaani

1 Ẹni ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha Gusù, gbọ́ pe Israeli gbà ọ̀na amí yọ; nigbana li o bá Israeli jà, o si mú ninu wọn ni igbekun. 2 Israeli si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, wipe, Bi iwọ ba fi awọn enia yi lé mi lọwọ nitõtọ, njẹ emi o run ilu wọn patapata. 3 OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma.

Ejò Idẹ

4 Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na. 5 Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa. 6 OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. 7 Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na. 8 OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè. 9 Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.

Láti Òkè Hori sí Àfonífojì Moabu

10 Awọn ọmọ Israeli si ṣi siwaju, nwọn si dó ni Obotu. 11 Nwọn si ṣi lati Obotu lọ, nwọn si dó si Iye-abarimu, li aginjù ti mbẹ niwaju Moabu, ni ìha ìla-õrùn. 12 Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si afonifoji Seredi. 13 Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori. 14 Nitorina ni a ṣe wi ninu iwé Ogun OLUWA pe, Ohun ti o ṣe li Okun Pupa, ati li odò Arnoni. 15 Ati ni iṣàn-odò nì ti o darí si ibujoko Ari, ti o si gbè ipinlẹ Moabu. 16 Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Beeri: eyinì ni kanga eyiti OLUWA sọ fun Mose pe, Pe awọn enia jọ, emi o si fun wọn li omi. 17 Nigbana ni Israeli kọrin yi pe: Sun jade iwọ kanga; ẹ ma kọrin si i: 18 Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana. 19 Ati Mattana nwọn lọ si Nahalieli: ati lati Nahalieli nwọn lọ si Bamotu: 20 Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.

Ìṣẹ́gun lórí Ọba Sihoni ati Ọba Ogu

21 Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe, 22 Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ. 23 Sihoni kò si jẹ ki Israeli ki o là àgbegbe rẹ̀ kọja: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo awọn enia rẹ̀ jọ, nwọn si jade tọ̀ Israeli lọ li aginjù, o si wá si Jahasi, o bá Israeli jà. 24 Israeli si fi oju idà kọlù u, o si gbà ilẹ rẹ̀ lati Arnoni lọ dé Jaboku, ani dé ti awọn ọmọ Ammoni; nitoripe ipinlẹ ti awọn ọmọ Ammoni lí agbara. 25 Israeli si gbà gbogbo ilunla wọnni: Israeli si joko ninu gbogbo ilunla ti awọn ọmọ Amori, ni Heṣboni, ati ni ilu rẹ̀ gbogbo. 26 Nitoripe Heṣboni ni ilunla Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ẹniti o ti bá ọba Moabu atijọ jà, ti o si gbà gbogbo ilẹ rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, titi dé Arnoni. 27 Nitorina awọn ti nkọrin owe a ma wipe, Wá si Heṣboni, jẹ ki a tẹ̀ ilunla Sihoni dó ki a si tun fi idi rẹ̀ mulẹ: 28 Nitoriti iná kan ti Heṣboni jade lọ, ọwọ́-iná kan lati ilunla Sihoni: o si run Ari ti Moabu, ati awọn oluwa ibi giga Arnoni. 29 Egbé ni fun iwọ, Moabu! Ẹ gbé, ẹnyin enia Kemoṣi: on ti fi awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bi isansa, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin bi igbekun, fun Sihoni ọba awọn ọmọ Amori. 30 Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba. 31 Bẹ̃li awọn ọmọ Israeli joko ni ilẹ awọn ọmọ Amori. 32 Mose si rán enia lọ ṣe amí Jaseri, nwọn si gbà ilu rẹ̀, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà nibẹ̀. 33 Nwọn si yipada, nwọn si gòke lọ li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade tọ̀ wọn lọ, on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, si ogun ni Edrei. 34 OLUWA si wi fun Mose pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe mo ti fi on lé ọ lọwọ, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀; ki iwọ ki o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni. 35 Bẹ̃ni nwọn si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, titi kò fi kù ọkan silẹ fun u lãye: nwọn si gbà ile rẹ̀.

Numeri 22

Ọba Moabu Ranṣẹ Pe Balaamu

1 AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko. 2 Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori. 3 Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli. 4 Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na. 5 O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi: 6 Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú. 7 Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u. 8 O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu. 9 Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ? 10 Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe, 11 Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ. 12 Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn. 13 Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ. 14 Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá. 15 Balaki si tun rán awọn ijoye si i, ti o si lí ọlá jù wọn lọ. 16 Nwọn tọ̀ Balaamu wá, nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Balaki ọmọ Sippori wi pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki ohun kan ki o di ọ lọwọ lati tọ̀ mi wá: 17 Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi. 18 Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla. 19 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i. 20 Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe. 21 Balaamu si dide li owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si bá awọn ijoye Moabu lọ.

Balaamu ati Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Rẹ̀

22 Ibinu Ọlọrun si rú nitoriti o lọ: angeli OLUWA si duro loju ọ̀na lati di i lọ̀na. Njẹ on gùn kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, awọn iranṣẹ rẹ̀ mejeji si wà pẹlu rẹ̀. 23 Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na. 24 Nigbana ni angeli OLUWA duro li ọna toro ọgbà-àjara meji, ogiri mbẹ ni ìha ihin, ati ogiri ni ìha ọhún. 25 Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o fún ara rẹ̀ mọ́ ogiri, o si fún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ogiri: on si tun lù u. 26 Angeli OLUWA si tun sun siwaju, o si tun duro ni ibi tõro kan, nibiti àye kò sí lati yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi. 27 Nigbati kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o wólẹ̀ labẹ Balaamu: ibinu Balaamu si rú pupọ̀, o si fi ọpá lu kẹtẹkẹtẹ na. 28 OLUWA si là kẹtẹkẹtẹ na li ohùn, o si wi fun Balaamu pe, Kini mo fi ṣe ọ, ti iwọ fi lù mi ni ìgba mẹta yi? 29 Balaamu si wi fun kẹtẹkẹtẹ na pe, Nitoriti iwọ fi mi ṣẹsin: idà iba wà li ọwọ́ mi, nisisiyi li emi iba pa ọ. 30 Kẹtẹkẹtẹ na si wi fun Balaamu pe, Kẹtẹkẹtẹ rẹ ki emi ṣe, ti iwọ ti ngùn lati ìgba ti emi ti ṣe tirẹ titi di oni? emi a ha ma ṣe si ọ bẹ̃ rí? On si dahùn wipe, Ndao. 31 Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ. 32 Angeli OLUWA si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi lù kẹtẹkẹtẹ rẹ ni ìgba mẹta yi? Kiyesi i, emi jade wá lati di ọ lọ̀na, nitori ọ̀na rẹ lòdi niwaju mi. 33 Kẹtẹkẹtẹ na si ri mi, o si yà fun mi ni ìgba mẹta yi: bikoṣe bi o ti yà fun mi, pipa ni emi iba pa ọ, emi a si dá on si. 34 Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada. 35 Angeli OLUWA si wi fun Balaamu pe, Ma bá awọn ọkunrin na lọ: ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o sọ. Bẹ̃ni Balaamu bá awọn ijoye Balaki lọ.

Balaki Lọ Pàdé Balaamu

36 Nigbati Balaki gbọ́ pe Balaamu dé, o jade lọ ipade rẹ̀ si Ilu Moabu, ti mbẹ ni àgbegbe Arnoni, ti iṣe ipẹkun ipinlẹ na. 37 Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi kò ha ranṣẹ kanjukanju si ọ lati pè ọ? ẽṣe ti iwọ kò fi tọ̀ mi wá? emi kò ha to lati sọ ọ di ẹni nla? 38 Balaamu si wi fun Balaki pe, Kiyesi i, emi tọ̀ ọ wá: emi ha lí agbara kan nisisiyi rára lati wi ohun kan? ọ̀rọ ti OLUWA fi si mi li ẹnu, on li emi o sọ. 39 Balaamu si bá Balaki lọ, nwọn si wá si Kiriati-husotu. 40 Balaki si rubọ akọmalu ati agutan, o si ranṣẹ si Balaamu, ati si awọn ijoye ti mbẹ pẹlu rẹ̀. 41 O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Balaki mú Balaamu, o si mú u wá si ibi giga Baali, ki o ba le ri apakan awọn enia na lati ibẹ̀ lọ.

Numeri 23

Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ tí Balaamu Sọ

1 BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin. 2 Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. 3 Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan. 4 Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. 5 OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ. 6 O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu. 7 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré. 8 Emi o ti ṣe fibú, ẹniti Ọlọrun kò fibú? tabi emi o si ti ṣe firé, ẹniti OLUWA kò firé? 9 Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède. 10 Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀! 11 Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata. 12 On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?

Àsọtẹ́lẹ̀ Keji tí Balaamu Sọ

13 Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ. 14 O si mú u wá si igbẹ Sofimu sori òke Pisga, o si mọ pẹpẹ meje, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. 15 On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi. 16 OLUWA si pade Balaamu, o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu, wipe, Tun pada tọ̀ Balaki lọ, ki o si wi bayi. 17 O si tọ̀ ọ wá, kiyesi i, o duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, ati awọn ijoye Moabu pẹlu rẹ̀. Balaki si bi i pe, Kini OLUWA sọ? 18 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Dide, Balaki, ki o si gbọ́; ki o si fetisi mi, iwọ ọmọ Sipporu: 19 Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ? 20 Kiyesi i, emi gbà aṣẹ ati sure: on si ti sure, emi kò si le yì i. 21 On kò ri ẹ̀ṣẹ ninu Jakobu, bẹ̃ni kò ri ibi ninu Israeli: OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ihó-ayọ ọba si mbẹ ninu wọn. 22 Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere. 23 Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe! 24 Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa. 25 Balaki si wi fun Balaamu pe, Kuku má fi wọn bú, bẹ̃ni ki o máṣe sure fun wọn rára. 26 Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe?

Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta Tí Balaamu Sọ

27 Balaki si wi fun Balaamu pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, emi o mú ọ lọ si ibomiran; bọya yio wù Ọlọrun ki iwọ ki o fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ. 28 Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù. 29 Balaamu si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọmalu meje ati àgbo meje fun mi nihin. 30 Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

Numeri 24

1 NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù. 2 Balaamu si gbé oju rẹ̀ soke o si ri Israeli dó gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; ẹmi Ọlọrun si wá sara rẹ̀. 3 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ sí nwi: 4 Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí. 5 Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli! 6 Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi. 7 Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke. 8 Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ. 9 O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú. 10 Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi. 11 Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá. 12 Balaamu si wi fun Balaki pe, Emi kò ti sọ fun awọn onṣẹ rẹ pẹlu ti iwọ rán si mi pe, 13 Bi Balaki tilẹ fẹ́ lati fi ile rẹ̀ ti o kún fun fadakà ati wurá fun mi, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA, lati ṣe rere tabi buburu lati inu ara mi wá; ṣugbọn eyiti OLUWA wi, eyina li emi o sọ?

Àsọtẹ́lẹ̀ Ìkẹyìn tí Balaamu Sọ

14 Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla. 15 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi: 16 Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí: 17 Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ. 18 Edomu yio si di iní, Seiri pẹlu yio si di iní, fun awọn ọtá rẹ̀; Israeli yio si ṣe iṣe-agbara. 19 Lati inu Jakobu li ẹniti yio ní ijọba yio ti jade wá, yio si run ẹniti o kù ninu ilunla. 20 Nigbati o si wò Amaleki, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Amaleki ni ekini ninu awọn orilẹ-ède; ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ ni ki o ṣegbé. 21 O si wò awọn ara Keni, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Agbara ni ibujoko rẹ̀, iwọ si tẹ́ itẹ́ rẹ sinu okuta. 22 Ṣugbọn a o run awọn ara Keni, titi awọn ara Aṣṣuri yio kó o lọ ni igbekùn. 23 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, A, tani yio wà, nigbati Ọlọrun yio ṣe eyi! 24 Awọn ọkọ̀ yio ti ebute Kittimu wá, nwọn o si pọn Aṣṣuri loju, nwọn o si pọn Eberi loju, on pẹlu yio si ṣegbé. 25 Balaamu si dide, o si lọ o si pada si ibujoko rẹ̀; Balaki pẹlu si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.

Numeri 25

Àwọn Ọmọ Israẹli ní Peori

1 ISRAELI si joko ni Ṣittimu, awọn enia na si bẹ̀rẹsi iṣe panṣaga pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu: 2 Nwọn si pe awọn enia na si ẹbọ oriṣa wọn; awọn enia na si jẹ, nwọn si tẹriba fun oriṣa wọn. 3 Israeli si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Baali-peoru: ibinu OLUWA si rú si Israeli. 4 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú gbogbo awọn olori awọn enia na, ki o si so wọn rọ̀ si õrùn niwaju OLUWA, ki imuna ibinu OLUWA ki o le yipada kuro lọdọ Israeli. 5 Mose si wi fun awọn onidajọ Israeli pe, Ki olukuluku nyin ki o pa awọn enia rẹ̀ ti o dàpọ mọ́ Baali-peoru. 6 Si kiyesi i, ọkan ninu awọn ọmọ Israeli wá o si mú obinrin Midiani kan tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ wá li oju Mose, ati li oju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ti nsọkun ni ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 7 Nigbati Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ri i, o dide lãrin ijọ, o si mú ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀; 8 O si tọ̀ ọkunrin Israeli na lọ ninu agọ́, o si fi gún awọn mejeji li agunyọ, ọkunrin Israeli na, ati obinrin na ni inu rẹ̀. Àrun si da lãrin awọn ọmọ Israeli. 9 Awọn ti o si kú ninu àrun na jẹ́ ẹgba mejila. 10 OLUWA si sọ fun Mose pe, 11 Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi. 12 Nitorina wipe, Kiyesi i, emi fi majẹmu alafia mi fun u. 13 Yio jẹ́ tirẹ̀ ati ti irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ani majẹmu iṣẹ-alufa titi-aiye; nitoriti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli. 14 Njẹ orukọ ọkunrin Israeli na ti a pa, ani ti a pa pẹlu obinrin Midiani na, a ma jẹ́ Simri, ọmọ Salu, olori ile kan ninu awọn ọmọ Simeoni. 15 Orukọ obinrin Midiani na ti a pa a si ma jẹ́ Kosbi, ọmọbinrin Suru; ti iṣe olori awọn enia kan, ati ti ile kan ni Midiani. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, 17 Yọ awọn ara Midiani lẹnu, ki o si kọlù wọn. 18 Nitoriti nwọn fi ẹ̀tan wọn yọ nyin lẹnu, eyiti nwọn tàn nyin niti ọ̀ran Peori, ati niti ọ̀ran Kosbi, ọmọ ijoye Midiani kan, arabinrin wọn, ẹniti a pa li ọjọ́ àrun nì niti ọ̀ran Peori.

Numeri 26

Ètò Ìkànìyàn Keji

1 O SI ṣe lẹhin àrun na, ni OLUWA sọ fun Mose ati fun Eleasari alufa ọmọ Aaroni pe, 2 Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli. 3 Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe, 4 Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá. 5 Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu: 6 Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi. 7 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin. 8 Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu. 9 Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà. 10 Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan. 11 Ṣugbọn awọn ọmọ Kora kò kú. 12 Awọn ọmọ Simeoni bi idile wọn: ti Nemueli, idile Nemueli: ti Jamini, idile Jamini: ti Jakini, idile Jakini: 13 Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu. 14 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba. 15 Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni: 16 Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri: 17 Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli. 18 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 19 Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani. 20 Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera. 21 Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu. 22 Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta. 23 Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa: 24 Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni. 25 Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun. 26 Awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: ti Seredi, idile Seredi: ti Eloni, idile Eloni: ti Jaleeli, idile Jaleeli. 27 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ mẹta o le ẹdẹgbẹta. 28 Awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn: Manasse ati Efraimu. 29 Awọn ọmọ Manasse: ti Makiri, idile Makiri: Makiri si bi Gileadi: ti Gileadi, idile awọn ọmọ Gileadi. 30 Wọnyi li awọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, idile Ieseri: ti Heleki, idile Heleki: 31 Ati ti Asrieli, idile Asrieli: ati ti Ṣekemu, idile Ṣekemu: 32 Ati Ṣemida, idile awọn ọmọ Ṣemida: ati ti Heferi, idile awọn ọmọ Heferi. 33 Selofehadi ọmọ Heferi kò si lí ọmọkunrin, bikọse ọmọbinrin: orukọ awọn ọmọbinrin Selofehadi a ma jẹ Mala, ati Noa, ati Hogla, Milka, ati Tirsa. 34 Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 35 Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani. 36 Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani. 37 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le ẹdẹgbẹta. Wọnyi li awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn. 38 Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu. 39 Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu. 40 Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani. 41 Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ. 42 Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn. 43 Gbogbo idile awọn ọmọ Ṣuhamu, gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo. 44 Ti awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn: ti Imna, idile awọn ọmọ Imna: ti Iṣfi, idile awọn ọmọ Iṣfi: ti Beria, idile awọn ọmọ Beria. 45 Ti awọn ọmọ Beria: ti Heberi, idile awọn ọmọ Heberi: ti Malkieli, idile awọn ọmọ Malkieli. 46 Orukọ ọmọ Aṣeri obinrin a si ma jẹ́ Sera. 47 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn; nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. 48 Ti awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn: ti Jaseeli, idile awọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, idile awọn ọmọ Guni: 49 Ti Jeseri, idile awọn ọmọ Jeseri: ti Ṣillemu, idile awọn ọmọ Ṣillemu. 50 Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje. 51 Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin. 52 OLUWA si sọ fun Mose pe, 53 Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ. 54 Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀. 55 Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i. 56 Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ. 57 Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari. 58 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu. 59 Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu. 60 Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari. 61 Ati Nadabu ati Abihu kú, nigbati nwọn mú iná ajeji wá siwaju OLUWA. 62 Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli. 63 Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. 64 Ṣugbọn ninu wọnyi kò sì ọkunrin kan ninu awọn ti Mose ati Aaroni alufa kà, nigbati nwọn kà awọn ọmọ Israeli li aginjù Sinai. 65 Nitoriti OLUWA ti wi fun wọn pe, Kíku ni nwọn o kú li aginjù. Kò si kù ọkunrin kan ninu wọn, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.

Numeri 27

Àwọn Ọmọbinrin Selofehadi

1 NIGBANA ni awọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile Manasse ọmọ Josefu wá: wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀; Mala, Noa, ati Hogla, ati Milka, ati Tirsa. 2 Nwọn si duro niwaju Mose, ati niwaju Eleasari alufa, ati niwaju awọn olori ati gbogbo ijọ, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, wipe, 3 Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin. 4 Ẽhaṣe ti orukọ, baba wa yio fi parẹ kuro ninu idile rẹ̀, nitoriti kò lí ọmọkunrin? Fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin baba wa. 5 Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA. 6 OLUWA si sọ fun Mose pe, 7 Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn. 8 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀. 9 Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. 10 Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀: 11 Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Yíyan Joṣua láti Rọ́pò Mose

12 OLUWA si sọ fun Mose pe, Gùn ori òke Abarimu yi lọ, ki o si wò ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli. 13 Nigbati iwọ ba ri i tán, a o si kó iwọ jọ pẹlu awọn enia rẹ, gẹgẹ bi a ti kó Aaroni arakunrin rẹ jọ. 14 Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.) 15 Mose si sọ fun OLUWA pe, 16 Jẹ ki OLUWA, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ki o yàn ọkunrin kan sori ijọ, 17 Ti yio ma ṣaju wọn jade lọ, ti yio si ma ṣaju wọn wọle wá, ti yio si ma sìn wọn lọ, ti yio si ma mú wọn bọ̀; ki ijọ enia OLUWA ki o máṣe dabi agutan ti kò lí oluṣọ. 18 OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkunrin ninu ẹniti ẹmi wà, ki o si fi ọwọ́ rẹ lé e lori; 19 Ki o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ; ki o si fi aṣẹ fun u li oju wọn. 20 Ki iwọ ki o si fi ninu ọlá rẹ si i lara, ki gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli ki o le gbà a gbọ́. 21 Ki on si duro niwaju Eleasari alufa, ẹniti yio bère fun u nipa idajọ Urimu niwaju OLUWA: nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o jade lọ, ati nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o wọle, ati on, ati gbogbo awọn ọmọ Israeli pẹlu rẹ̀, ani gbogbo ijọ. 22 Mose si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o si mú Joṣua, o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ: 23 O si fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori, o si fi aṣẹ fun u, bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.

Numeri 28

Ẹbọ Àtìgbàdégbà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn. 3 Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Eyi li ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti ẹnyin o ma múwa fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku li ojojumọ́, fun ẹbọ sisun igbagbogbo. 4 Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ; 5 Ati idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro gigún pò. 6 Ẹbọ sisun igbagbogbo ni, ti a ti lanasilẹ li òke Sinai fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 7 Ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ki o jẹ́ idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: ni ibi-mimọ ni ki iwọ da ọti lile nì silẹ fun OLUWA fun ẹbọ ohunmimu. 8 Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ: bi ẹbọ ohunjijẹ ti owurọ̀, ati bi ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ni ki iwọ ki o ṣe, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ìsinmi

9 Ati li ọjọ́-isimi akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀: 10 Eyi li ẹbọ sisun ọjọjọ́ isimi, pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 11 Ati ni ìbẹrẹ òṣu nyin ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun kan si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku; 12 Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ: 13 Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun ọdọ-agutan kan fun ẹbọ ohunjijẹ; fun ẹbọ sisun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 14 Ki ẹbọ ohunmimu wọn ki o jẹ́ àbọ òṣuwọn hini ti ọti-waini fun akọmalu kan, ati idamẹta òṣuwọn hini fun àgbo kan, ati idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: eyi li ẹbọ sisun oṣuṣù ni gbogbo oṣù ọdún. 15 A o si fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ si OLUWA; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

Ẹbọ Àjọ̀dún Àjọ Àìwúkàrà

16 Ati li ọjọ́ kẹrinla oṣù kini, ni irekọja OLUWA. 17 Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na yi li ajọ: ni ijọ́ meje ni ki a fi jẹ àkara alaiwu. 18 Li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: 19 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ kan ti a fi iná ṣe, ẹbọ sisun si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdun kan: ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin. 20 Ẹbọ ohunjijẹ wọn iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn ni ki ẹnyin ki o múwa fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo na. 21 Ati idamẹwa òṣuwọn ni ki iwọ ki o múwa fun ọdọ-agutan kan, fun gbogbo ọdọ-agutan mejeje; 22 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin. 23 Ki ẹnyin ki o mú wọnyi wá pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀, ti iṣe ti ẹbọ sisun igbagbogbo. 24 Bayi ni ki ẹnyin rubọ li ọjọjọ́, jalẹ ni ijọ́ mejeje, onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: ki a ru u pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 25 Ati ni ijọ́ keje ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.

Ẹbọ Àjọ̀dún Ìkórè

26 Li ọjọ́ akọ́so pẹlu, nigbati ẹnyin ba mú ẹbọ ohunjijẹ titun wá fun OLUWA, lẹhin ọsẹ̀ nyin wọnni, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: 27 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu meji, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan, ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA; 28 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, 29 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje; 30 Ati obukọ kan, lati ṣètutu fun nyin. 31 Ki ẹnyin ki o ru wọn pẹlu ẹbọ sisun igba-gbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ (ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin), ati ẹbọ ohunmimu wọn.

Numeri 29

Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun

1 ATI li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù na ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: ọjọ́ ifunpe ni fun nyin. 2 Ki ẹnyin ki o si fi ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA: 3 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, 4 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje: 5 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin; 6 Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù

7 Ki ẹnyin ki o si ní apejọ mimọ́ ni ijọ́ kẹwa oṣù keje na yi; ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: 8 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin: 9 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji ọsuwọn fun àgbo kan, 10 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje: 11 Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn. 12 Ati ni ijọ́ kẹdogun oṣù keje, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje: 13 Ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ sisun kan, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu mẹtala, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan; ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku: 14 Ati ẹbọ ohun-jijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, bẹ̃ni fun akọmalu mẹtẹtala, idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, bẹ̃ni fun àgbo mejeji, 15 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mẹrẹrinla: 16 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 17 Ati ni ijọ́ keji ni ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo meji, ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku rubọ: 18 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 19 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn. 20 Ati ni ijọ́ kẹta akọmalu mọkanla, àgbo meji, akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku; 21 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 22 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 23 Ati ni ijọ́ kẹrin akọmalu mẹwa, àgbo meji, ati ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 24 Ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 25 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 26 Ati ni ijọ́ karun akọmalu mẹsan, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 27 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 28 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 29 Ati ni ijọ́ kẹfa akọmalu mẹjọ, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 30 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 31 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 32 Ati ni ijọ́ keje akọmalu meje, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku: 33 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 34 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 35 Ni ijọ́ kẹjọ ki ẹnyin ki o ní ajọ ti o ni ironu: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan. 36 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku: 37 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na: 38 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀. 39 Ẹbọ wọnyi ni ki ẹnyin ki o ru si OLUWA li ajọ nyin, pẹlu ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ọrẹ-atinuwa nyin, fun ẹbọ sisun nyin, ati fun ẹbọ ohunjijẹ nyin, ati fun ẹbọ ohun mimu nyin, ati fun ẹbọ alafia nyin. 40 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ fun Mose.

Numeri 30

Ìlànà nípa Ẹ̀jẹ́ Jíjẹ́

1 MOSE si sọ fun awọn olori awọn ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ. 2 Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade. 3 Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀; 4 Ti baba rẹ̀ si gbọ́ ẹjẹ́ rẹ̀, ati ìde rẹ̀ ti o fi dè ara rẹ̀, ti baba rẹ̀ ba si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i; njẹ ki gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ki o duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. 5 Ṣugbọn bi baba rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; kò sí ọkan ninu ẹjẹ́ rẹ̀, tabi ninu ìde ti o fi dè ara rẹ̀, ti yio duro: OLUWA yio si darijì i, nitoriti baba rẹ̀ kọ̀ fun u. 6 Bi o ba si kúku li ọkọ, nigbati o jẹ́ ẹjẹ́, tabi ti o sọ̀rọ kan lati ẹnu rẹ̀ jade, ninu eyiti o fi dè ara rẹ̀ ni ìde; 7 Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ẹjẹ́ rẹ̀ yio duro, ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. 8 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ on o mu ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́ ati ohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade, eyiti o fi dè ara rẹ̀ dasan: OLUWA yio si darijì i. 9 Ṣugbọn gbogbo ẹjẹ́ opó, ati ti obinrin ti a kọ̀silẹ, ti nwọn fi dè ara wọn, yio wà lọrùn rẹ̀. 10 Bi o ba si jẹjẹ́ ni ile ọkọ rẹ̀, tabi ti o si fi ibura dè ara rẹ̀ ni ìde, 11 Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i, ti kò si kọ̀ fun u: njẹ gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ni yio duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. 12 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba sọ wọn dasan patapata li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ohunkohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade nipasẹ̀ ẹjẹ́ rẹ̀, tabi nipasẹ̀ ìde ọkàn rẹ̀, ki yio duro: ọkọ rẹ̀ ti sọ wọn dasan; OLUWA yio si darijì i. 13 Gbogbo ẹjẹ́ ati ibura ìde lati fi pọ́n ara loju, ọkọ rẹ̀ li o le mu u duro, o si le sọ ọ dasan. 14 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i patapata lati ọjọ́ dé ọjọ́; njẹ o fi mu gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ duro, tabi gbogbo ìde rẹ̀ ti mbẹ lara rẹ̀; o mu wọn duro, nitoriti o pa ẹnu rẹ̀ mọ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́. 15 Ṣugbọn bi o ba sọ wọn dasan, lẹhin igbati o gbọ́; njẹ on ni yio rù ẹ̀ṣẹ obinrin na. 16 Wọnyi ni ìlana ti OLUWA palaṣẹ fun Mose, lãrin ọkunrin ati aya rẹ̀, lãrin baba ati ọmọbinrin rẹ̀, ti iṣe ewe ninu ile baba rẹ̀.

Numeri 31

Wọ́n Dojú Ogun Mímọ́ kọ Midiani

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Gbẹsan awọn ọmọ Israeli lara awọn ara Midiani: lẹhin eyinì ni a o kó ọ jọ pẹlu awọn enia rẹ. 3 Mose si sọ fun awọn enia na pe, Ki ninu nyin ki o hamọra ogun, ki nwọn ki o si tọ̀ awọn ara Midiani lọ, ki nwọn ki o si gbẹsan OLUWA lara Midiani. 4 Ninu ẹ̀ya kọkan ẹgbẹrun enia, ni gbogbo ẹ̀ya Israeli, ni ki ẹnyin ki o rán lọ si ogun na. 5 Bẹ̃ni nwọn si yàn ninu awọn ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, ẹgba mẹfa enia ti o hamọra ogun. 6 Mose si rán wọn lọ si ogun na, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, awọn ati Finehasi ọmọ Eleasari alufa si ogun na, ti on ti ohunèlo ibi-mimọ́, ati ipè wọnni li ọwọ́ rẹ̀ lati fun. 7 Nwón si bá awọn ara Midiani jà, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose; nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin. 8 Nwọn si pa awọn ọba Midiani, pẹlu awọn iyokù ti a pa; eyinì ni Efi, ati Rekemu, ati Suru, ati Huri, ati Reba, ọba Midiani marun: Balaamu ọmọ Beoru ni nwọn si fi idà pa. 9 Awọn ọmọ Israeli si mú gbogbo awọn obinrin Midiani ni igbẹsin, ati awọn ọmọ kekere wọn, nwọn si kó gbogbo ohunọ̀sin wọn, ati gbogbo agboẹran wọn, ati gbogbo ẹrù wọn. 10 Nwọn si fi iná kun gbogbo ilu wọn ninu eyiti nwọn ngbé, ati gbogbo ibudó wọn. 11 Nwọn si kó gbogbo ikogun wọn, ati gbogbo ohun-iní, ati enia ati ẹran. 12 Nwọn si kó igbẹsin, ati ohun-iní, ati ikogun na wá sọdọ Mose, ati Eleasari alufa, ati sọdọ ijọ awọn ọmọ Israeli, si ibudó ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, ti mbẹ lẹba Jordani leti Jeriko.

Àwọn Ọmọ Ogun Pada Wálé

13 Ati Mose, ati Eleasari alufa, ati gbogbo awọn olori ijọ, jade lọ ipade wọn lẹhin ibudó. 14 Mose si binu si awọn olori ogun na, pẹlu awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati balogun ọrọrún, ti o ti ogun na bọ̀. 15 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ da gbogbo awọn obinrin si? 16 Kiyesi i, nipaṣe ọ̀rọ Balaamu awọn wọnyi li o mu awọn ọmọ Israeli dẹ̀ṣẹ si OLUWA niti ọ̀ran Peori, ti àrun si fi wà ninu ijọ OLUWA. 17 Njẹ nitorina, ẹ pa gbogbo ọkunrin ninu awọn ọmọ wẹ́wẹ, ki ẹ si pa gbogbo awọn obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀. 18 Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọbinrin kekeké ti nwọn kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀, ni ki ẹnyin dasi fun ara nyin. 19 Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje. 20 Ki ẹnyin si fọ̀ gbogbo aṣọ nyin mọ́, ati gbogbo ohun ti a fi awọ ṣe, ati ohun gbogbo iṣẹ irun ewurẹ, ati ohun gbogbo ti a fi igi ṣe. 21 Eleasari alufa si wi fun awọn ologun ti nwọn lọ si ogun na pe, Eyi ni ilana ofin ti OLUWA filelẹ li aṣẹ fun Mose. 22 Kìki wurà, ati fadakà, ati idẹ ati irin, ati tanganran, ati ojé, 23 Gbogbo ohun ti o le kọja ninu iná, ni ki ẹnyin ki o mu là iná já yio si di mimọ́; ṣugbọn a o fi omi ìyasapakan wẹ̀ ẹ mọ́: ati gbogbo ohun ti kò le kọja ninu iná ni ki a mu là inu omi. 24 Ki ẹnyin ki o si fọ̀ aṣọ nyin ni ijọ́ keje, ẹnyin o si di mimọ́, lẹhin eyinì li ẹnyin o si wá sinu ibudó.

Pípín Ìkógun

25 OLUWA si sọ fun Mose pe, 26 Kà iye ikogun ti a kó, ti enia ati ti ẹran, iwọ ati Eleasari alufa, ati awọn olori ile baba ijọ: 27 Ki o si pín ikogun na si ipa meji; lãrin awọn ologun, ti o jade lọ si ogun na, ati lãrin gbogbo ijọ. 28 Ki o si gbà ohun idá ti OLUWA lọwọ awọn ologun ti nwọn jade lọ si ogun na: ọkan ninu ẹdẹgbẹta, ninu awọn enia, ati ninu malu, ati ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran: 29 Gbà a ninu àbọ ti wọn, ki o si fi i fun Eleasari alufa, fun ẹbọ igbesọsoke OLUWA. 30 Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA. 31 Ati Mose ati Eleasari alufa si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 32 Ati ikogun ti o kù ninu ohun-iní ti awọn ologun kó, o jẹ́ ọkẹ mẹrinlelọgbọ̀n o din ẹgbẹdọgbọ̀n agutan, 33 Ẹgba mẹrindilogoji malu, 34 Ọkẹ mẹta o le ẹgbẹrun kẹtẹkẹtẹ, 35 Ati enia ninu awọn obinrin ti kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dàpọ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun. 36 Ati àbọ ti iṣe ipín ti awọn ti o jade lọ si ogun, o jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan ni iye: 37 Idá ti OLUWA ninu agutan wọnni jẹ́ ẹdẹgbẹrin o din mẹdọgbọ̀n. 38 Ati malu jẹ́ ẹgba mejidilogun; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ mejilelãdọrin. 39 Kẹtẹkẹtẹ si jẹ́ ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgọta o le ọkan. 40 Awọn enia si jẹ́ ẹgba mẹjọ; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgbọ̀n o le meji. 41 Mose si fi idá ti ẹbọ igbesọsoke OLUWA fun Eleasari alufa, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 42 Ati ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, ti Mose pín kuro ninu ti awọn ọkunrin ti o jagun na, 43 (Njẹ àbọ ti ijọ jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan, 44 Ati ẹgba mejidilogun malu. 45 Ati ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta kẹtẹkẹtẹ. 46 Ati ẹgba mẹjọ enia;) 47 Ani ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, Mose mú ipín kan ninu ãdọta, ati ti enia ati ti ẹran, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 48 Ati awọn olori ti o wà lori ẹgbẹgbẹrun ogun na, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati awọn balogun ọrọrún, wá sọdọ Mose: 49 Nwọn si wi fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kà iye awọn ologun, ti mbẹ ni itọju wa, ọkunrin kan ninu wa kò si din. 50 Nitorina li awa ṣe mú ọrẹ-ebọ wá fun OLUWA, ohunkohun ti olukuluku ri, ohun ọ̀ṣọ wurà, ẹ̀wọn, ati jufù, ati oruka-àmi, ati oruka-etí, ati ìlẹkẹ, lati fi ṣètutu fun ọkàn wa niwaju OLUWA. 51 Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ wọn, ani gbogbo ohun-iṣẹ ọsọ́. 52 Ati gbogbo wurà ẹbọ igbesọsoke ti nwọn múwa fun OLUWA, lati ọdọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lati ọdọ awọn balogun ọrọrún, o jẹ́ ẹgba mẹjọ o le ẹdẹgbẹrin o le ãdọta ṣekeli. 53 (Nitoripe awọn ologun ti kó ẹrù, olukuluku fun ara rẹ̀.) 54 Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lọwọ awọn balogun ọrọrún nwọn si mú u wá sinu agọ́ ajọ, ni iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA.

Numeri 32

Àwọn Ẹ̀yà Ìlà Oòrùn Jọdani

1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni; 2 Awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni si wá, nwọn si sọ fun Mose, ati fun Eleasari alufa ati fun awọn olori ijọ pe, 3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni. 4 Ilẹ na ti OLUWA ti kọlù niwaju ijọ Israeli, ilẹ ohunọ̀sin ni, awa iranṣẹ rẹ si ní ohunọ̀sin. 5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ. 6 Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi? 7 Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn? 8 Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na. 9 Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn. 10 Ibinu Ọlọrun si rú si wọn nigbana, o si bura, wipe, 11 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti o gòke lati Egipti wá, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki yio ri ilẹ na ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu: nitoriti nwọn kò tẹle mi lẹhin patapata. 12 Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne ọmọ Kenissi, ati Joṣua ọmọ Nuni: nitoripe awọn li o tẹle OLUWA lẹhin patapata. 13 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si mu wọn rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, titi gbogbo iran na, ti o ṣe buburu li oju OLUWA fi run. 14 Si kiyesi i, ẹnyin dide ni ipò baba nyin, iran ẹ̀lẹṣẹ, lati mu ibinu gbigbona OLUWA pọ̀ si i si Israeli. 15 Nitoripe bi ẹnyin ba yipada kuro lẹhin rẹ̀, on o si tun fi wọn silẹ li aginjù; ẹnyin o si run gbogbo awọn enia yi. 16 Nwọn si sunmọ ọ wipe, Awa o kọ́ ile-ẹran nihinyi fun ohunọ̀sin wa, ati ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ wa: 17 Ṣugbọn awa tikala wa yio di ihamọra wa giri, niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa o fi mú wọn dé ipò wọn: awọn ọmọ wẹ́wẹ wa yio si ma gbé inu ilu olodi nitori awọn ara ilẹ na. 18 Awa ki yio pada bọ̀ si ile wa, titi olukuluku awọn ọmọ Israeli yio fi ní ilẹ-iní rẹ̀. 19 Nitoripe awa ki yio ní ilẹ-iní pẹlu wọn ni ìha ọhún Jordani, tabi niwaju: nitoriti awa ní ilẹ-iní wa ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla õrùn. 20 Mose si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin o ba ṣe eyi; bi ẹnyin o ba di ihamọra niwaju OLUWA lọ si ogun, 21 Bi gbogbo nyin yio ba gòke Jordani ni ihamora niwaju OLUWA, titi yio fi lé awọn ọtá rẹ̀ kuro niwaju rẹ̀, 22 Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA. 23 Ṣugbọn bi ẹnyin ki yio ba ṣe bẹ̃, kiyesi i, ẹnyin dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, ẹ̀ṣẹ nyin yio fi nyin hàn. 24 Ẹ kọ́ ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati agbo fun agutan nyin; ki ẹ si ṣe eyiti o ti ẹnu nyin jade wa. 25 Awọn ọmọ Gadi, ati awọn Reubeni si sọ fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ yio ṣe bi oluwa mi ti fi aṣẹ lelẹ. 26 Awọn ọmọ wẹ́wẹ wa, ati awọn aya wa, agbo-ẹran wa, ati gbogbo ohunọsìn wa yio wà nibẹ̀ ni ilu Gileadi: 27 Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ yio gòke odò, olukuluku ni ihamọra ogun, niwaju OLUWA lati jà, bi oluwa mi ti wi. 28 Mose si paṣẹ fun Eleasari alufa, ati fun Joṣua ọmọ Nuni, ati fun awọn olori ile baba awọn ẹ̀ya ọmọ Israeli, nipa ti wọn. 29 Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní: 30 Ṣugbọn bi nwọn kò ba fẹ́ ba nyin gòke odò ni ihamọra, njẹ ki nwọn ki o ní iní lãrin nyin ni ilẹ Kenaani. 31 Ati awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni dahùn, wipe, Bi OLUWA ti wi fun awọn iranṣẹ rẹ, bẹ̃li awa o ṣe. 32 Awa o gòke lọ ni ihamọra niwaju OLUWA si ilẹ Kenaani, ki iní wa ni ìha ihin Jordani ki o le jẹ́ ti wa. 33 Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká. 34 Awọn ọmọ Gadi si kọ́ Didoni, ati Atarotu, ati Aroeri; 35 Ati Atrotu-ṣofani, ati Jaseri, ati Jogbeha; 36 Ati Beti-nimra, ati Beti-harani, ilu olodi, ati agbo fun agutan. 37 Awọn ọmọ Reubeni si kọ́ Heṣboni, ati Eleale, ati Kiriataimu. 38 Ati Nebo, ati Baali-meoni, (nwọn pàrọ orukọ wọn,) ati Sibma: nwọn si sọ ilu ti nwọn kọ́ li orukọ miran. 39 Awọn ọmọ Makiri ọmọ Manase si lọ si Gileadi, nwọn si gbà a, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà ninu rẹ̀. 40 Mose si fi Gileadi fun Makiri ọmọ Manase; o si joko ninu rẹ̀. 41 Jairi ọmọ Manasse, si lọ, o si gbà awọn ilu wọn, o si sọ wọn ni Haffotu-jairi. 42 Noba si lọ, o si gbà Kenati, ati awọn ileto rẹ̀, o si sọ ọ ni Noba, nipa orukọ ara rẹ̀.

Numeri 33

Ìrìn Àjò láti Ijipti sí Moabu

1 WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni. 2 Mose si kọwe ijadelọ wọn gẹgẹ bi ìrin wọn, nipa aṣẹ OLUWA; wọnyi si ni ìrin wọn gẹgẹ bi ijadelọ wọn. 3 Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti. 4 Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ. 5 Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu. 6 Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù. 7 Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu. 8 Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara. 9 Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀. 10 Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa. 11 Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini. 12 Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka. 13 Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi. 14 Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu. 15 Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai. 16 Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa. 17 Nwọn si ṣí kuro ni Kibrotu-hattaafa, nwọn si dó si Haserotu. 18 Nwọn si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si Ritma. 19 Nwọn si ṣí kuro ni Ritma, nwọn si dó si Rimmon-peresi. 20 Nwọn si ṣí kuro ni Rimmon-peresi, nwọn si dó si Libna. 21 Nwọn si ṣí kuro ni Libna, nwọn si dó si Rissa. 22 Nwọn si ṣí kuro ni Rissa, nwọn si dó si Kehelata. 23 Nwọn si ṣí kuro ni Kehelata, nwọn si dó si òke Ṣeferi. 24 Nwọn si ṣí kuro ni òke Ṣeferi, nwọn si dó si Harada. 25 Nwọn si ṣí kuro ni Harada, nwọn si dó si Makhelotu. 26 Nwọn si ṣí kuro ni Makhelotu, nwọn si dó si Tahati. 27 Nwọn si ṣí kuro ni Tahati, nwọn si dó si Tera. 28 Nwọn si ṣí kuro ni Tera, nwọn si dó si Mitka. 29 Nwọn si ṣí kuro ni Mitka, nwọn si dó si Haṣmona. 30 Nwọn si ṣí kuro ni Haṣmona, nwọn si dó si Moserotu. 31 Nwọn si ṣí kuro ni Moserotu, nwọn si dó si Bene-jaakani. 32 Nwọn si ṣí kuro ni Bene-jaakani, nwọn si dó si Hori-haggidgadi. 33 Nwọn si ṣí kuro ni Hori-haggidgadi, nwọn si dó si Jotbata. 34 Nwọn si ṣí kuro ni Jotbata, nwọn si dó si Abrona. 35 Nwọn si ṣí kuro ni Abrona, nwọn si dó si Esion-geberi. 36 Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi), 37 Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu. 38 Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun. 39 Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún o le mẹta nigbati o kú li òke Hori. 40 Ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha gusù ni ilẹ Kenaani, o gburó pe awọn ọmọ Israeli mbọ̀. 41 Nwọn si ṣí kuro ni òke Hori, nwọn si dó si Salmona. 42 Nwọn si ṣí ni Salmona, nwọn si dó si Punoni. 43 Nwọn si ṣí kuro ni Punoni, nwọn si dó si Obotu. 44 Nwọn si ṣí kuro ni Obotu, nwọn si dó si Iye-abarimu, li àgbegbe Moabu. 45 Nwọn si ṣí kuro ni Iyimu, nwọn si dó si Dibon-gadi. 46 Nwọn si ṣí kuro ni Dibon-gadi, nwọn si dó si Almon-diblataimu. 47 Nwọn si ṣí kuro ni Almon-diblataimu, nwọn si dó si òke Abarimu, niwaju Nebo. 48 Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. 49 Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.

Ìlànà Nípa Líla Odò Jọdani Kọjá

50 OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe, 51 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani: 52 Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ: 53 Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i. 54 Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i. 55 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé. 56 Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.

Numeri 34

Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,) 3 Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn: 4 Ki opinlẹ nyin ki o si yí lati gusù wá si ìgoke Akrabbimu, ki o si kọja lọ si Sini: ati ijadelọ rẹ̀ ki o jẹ́ ati gusù lọ si Kadeṣi-barnea, ki o si dé Hasari-addari, ki o si kọja si Asmoni: 5 Ki opinlẹ rẹ̀ ki o si yiká lati Asmoni lọ dé odò Egipti, okun ni yio si jẹ́ opin rẹ̀. 6 Ati opinlẹ ìha ìwọ-õrùn, ani okun nla ni yio jẹ́ opin fun nyin: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ìwọ-õrùn fun nyin. 7 Eyi ni yio si jẹ́ opinlẹ ìha ariwa fun nyin: lati okun nla lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ òke Hori: 8 Lati òke Hori lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ ati wọ̀ Hamati; ijadelọ opinlẹ na yio si jẹ́ Sedadi: 9 Opinlẹ rẹ yio si dé Sifroni, ati ijadelọ rẹ̀ yio dé Hasari-enani: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ariwa nyin. 10 Ki ẹnyin ki o si sàmi si opinlẹ nyin ni ìha ìla-õrùn lati Hasari-enani lọ dé Ṣefamu: 11 Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn. 12 Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri. 13 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi ni ilẹ na ti ẹnyin o fi keké gbà ni iní, ti OLUWA paṣẹ lati fi fun ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya nì: 14 Fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi ile baba wọn, ati ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi ile baba wọn ti gbà; àbọ ẹ̀ya Manasse si ti gbà, ipín wọn: 15 Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.

Àwọn Olórí tí Yóo Pín Ilẹ̀ náà

16 OLUWA si sọ fun Mose pe, 17 Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni. 18 Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní. 19 Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne. 20 Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu. 21 Ni ẹ̀ya Benjamini, Elidadi ọmọ Kisloni. 22 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Dani, Bukki ọmọ Jogli. 23 Olori awọn ọmọ Josefu: ni ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse, Hannieli ọmọ Efodu: 24 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu, Kemueli ọmọ Ṣiftani. 25 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni, Elisafani ọmọ Parnaki. 26 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari, Paltieli ọmọ Assani. 27 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri, Ahihudu ọmọ Ṣelomi. 28 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali, Pedaheli ọmọ Ammihudu. 29 Awọn wọnyi li ẹniti OLUWA paṣẹ fun lati pín iní na fun awọn ọmọ Israeli ni ilẹ Kenaani.

Numeri 35

Àwọn Ìlú tí A Fún Àwọn Ọmọ Lefi

1 OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe, 2 Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o fi ilu fun awọn ọmọ Lefi ninu ipín ilẹ-iní wọn, lati ma gbé; ki ẹnyin ki o si fi ẹbẹba-ilu fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnni yi wọn ká. 3 Ki nwọn ki o ní ilu lati ma gbé; ati ẹbẹba-ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn, ati fun ohun-iní wọn, ati fun gbogbo ẹran wọn. 4 Ati ẹbẹba-ilu, ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, lati odi ilu lọ sẹhin rẹ̀ ki o jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ yiká. 5 Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn. 6 Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn. 7 Gbogbo ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi ki o jẹ́ mejidilãdọta: wọnyi ni ki ẹnyin fi fun wọn pẹlu ẹbẹba wọn. 8 Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.

Àwọn Ìlú-Ààbò

9 OLUWA si sọ fun Mose pe, 10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ Kenaani; 11 Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀. 12 Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ. 13 Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin. 14 Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo. 15 Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀. 16 Ṣugbọn bi o ba fi ohunèlo irin lù u, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na. 17 Ati bi o ba sọ okuta lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: a o pa apania na. 18 Tabi bi o ba fi ohun-èlo igi lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na. 19 Agbẹsan ẹ̀jẹ tikalarẹ̀ ni ki o pa apania na: nigbati o ba bá a, ki o pa a. 20 Ṣugbọn bi o ba ṣepe o fi irira gún u, tabi ti o ba sọ nkan lù u, lati ibuba wá, ti on si kú; 21 Tabi bi o nṣe ọtá, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ lù u, ti on si kú: ẹniti o lù u nì pipa li a o pa a; nitoripe apania li on: agbẹsan ẹ̀jẹ ni ki o pa apania na, nigbati o ba bá a. 22 Ṣugbọn bi o ba fi nkan gún u lojiji laiṣe ọtá, tabi ti o sọ ohunkohun lù u laiba dè e, 23 Tabi okuta kan li o sọ, nipa eyiti enia le fi kú, ti kò ri i, ti o si sọ ọ lù u, ti on si kú, ti ki ṣe ọtá rẹ̀, ti kò si wá ibi rẹ̀: 24 Nigbana ni ki ijọ ki o ṣe idajọ lãrin ẹniti o pa enia ati agbẹsan ẹ̀jẹ na, gẹgẹ bi idajọ wọnyi: 25 Ki ijọ ki o si gbà ẹniti o pani li ọwọ́ agbẹsan ẹ̀jẹ, ki ijọ ki o si mú u pada lọ si ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si: ki o si ma gbé ibẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa, ti a fi oróro mimọ́ yàn. 26 Ṣugbọn bi apania na ba ṣèṣi jade lọ si opinlẹ ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si; 27 Ti agbẹsan ẹ̀jẹ na si ri i lẹhin opinlẹ ilu àbo rẹ̀, ti agbẹsan ẹ̀jẹ si pa apania na; on ki yio jẹbi ẹ̀jẹ: 28 Nitoripe on iba joko ninu ilu àbo rẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa: ati lẹhin ikú olori alufa ki apania na ki o pada lọ si ilẹ iní rẹ̀. 29 Ohun wọnyi ni o si jẹ́ ìlana idajọ fun nyin ni iraniran nyin ni ibujoko nyin gbogbo. 30 Ẹnikẹni ti o ba pa enia, lati ẹnu awọn ẹlẹri wá li a o pa apania na: ṣugbọn ẹlẹri kanṣoṣo ki yio jẹri si ẹnikan lati pa a. 31 Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o máṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹmi apania, ti o jẹbi ikú: ṣugbọn pipa ni ki a pa a. 32 Ki ẹnyin ki o má si ṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹniti o salọ si ilu àbo rẹ̀, pe ki on ki o tun pada lọ ijoko ni ilẹ na, titi di ìgba ikú alufa. 33 Ẹnyin kò si gbọdọ bà ilẹ na jẹ́ ninu eyiti ẹnyin ngbé: nitoripe ẹ̀jẹ ama bà ilẹ jẹ́: a kò si le ṣètutu fun ilẹ nitori ẹ̀je ti a ta sinu rẹ̀, bikoṣe nipa ẹ̀jẹ ẹniti o ta a. 34 Iwọ kò si gbọdọ sọ ilẹ na di alaimọ́, ninu eyiti ẹnyin o joko, ninu eyiti emi ngbé: nitori Emi JEHOFA ni ngbé inu awọn ọmọ Israeli.

Numeri 36

Ogún Àwọn Obinrin Abilékọ

1 AWỌN baba àgba ti idile awọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile awọn ọmọ Josefu, sunmọtosi, nwọn si sọ niwaju Mose, ati niwaju awọn olori, awọn baba àgba awọn ọmọ Israeli: 2 Nwọn si wipe, OLUWA ti paṣẹ fun oluwa mi lati fi keké pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli ni iní: a si fi aṣẹ fun oluwa mi lati ọdọ OLUWA wá lati fi ilẹiní Selofehadi arakunrin wa fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin. 3 Bi a ba si gbé wọn niyawo fun ẹnikan ninu awọn ọmọkunrin ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli miran, nigbana ni a o gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní awọn baba wa, a o si fi kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà a kuro ninu ipín ilẹ-iní ti wa. 4 Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa. 5 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, pe, Ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu fọ̀ rere. 6 Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si. 7 Bẹ̃ni ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli ki yio yi lati ẹ̀ya de ẹ̀ya: nitori ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le faramọ́ ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba rẹ̀: 8 Ati gbogbo awọn ọmọbinrin, ti o ní ilẹ-iní ninu ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, ki o ṣe aya fun ọkan ninu idile ẹ̀ya baba rẹ̀, ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le ma jogún ilẹ-iní awọn baba rẹ̀. 9 Bẹ̃ni ki ilẹ-iní ki o máṣe yi lati ẹ̀ya kan lọ si ẹ̀ya keji; ṣugbọn ki olukuluku ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli ki o faramọ́ ilẹ-iní tirẹ̀. 10 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe: 11 Nitoripe a gbé Mala, Tirsa, ati Hogla, ati Milka, ati Noa, awọn ọmọbinrin Selofehadi niyawo fun awọn ọmọ arakunrin baba wọn. 12 A si gbé wọn niyawo sinu idile awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu, ilẹ-ini wọn si duro ninu ẹ̀ya idile baba wọn. 13 Wọnyi ni aṣẹ ati idajọ ti OLUWA palaṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ọwọ́ Mose, ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.

Deuteronomi 1

Ìwé Karun-un Mose, tí à ń pè ní Diutaronomi

1 WỌNYI li ọ̀rọ ti Mose sọ fun gbogbo Israeli ni ìha ihin Jordani li aginjù, ni pẹtẹlẹ̀ ti o kọjusi Okun Pupa, li agbedemeji Parani, ati Tofeli, ati Labani, ati Haserotu, ati Disahabu. 2 Ijọ́ mọkanla ni lati Horebu wá li ọ̀na òke Seiri dé Kadeṣi-barnea. 3 O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn; 4 Lẹhin igbati o pa Sihoni tán ọba awọn ọmọ Amori, ti o ngbé Heṣboni, ati Ogu ọba Baṣani, ti o ngbé Aṣtarotu, ni Edrei: 5 Ni ìha ihin Jordani, ni ilẹ Moabu, on ni Mose bẹ̀rẹsi isọ asọye ofin yi, wipe, 6 OLUWA Ọlọrun wa sọ fun wa ni Horebu, wipe, Ẹ gbé ori òke yi pẹ to: 7 Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate. 8 Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.

Mose Yan Àwọn Adájọ́

9 Mo si sọ fun nyin ni ìgba na pe, Emi nikan kò le rù ẹrù nyin: 10 OLUWA Ọlọrun nyin ti mu nyin bisi i, si kiyesi i, li oni ẹnyin dabi irawọ oju-ọrun fun ọ̀pọ. 11 Ki OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin ki o fi kún iye nyin ni ìgba ẹgbẹrun, ki o si busi i fun nyin, bi o ti ṣe ileri fun nyin! 12 Emi o ti ṣe le nikan rù inira nyin, ati ẹrù nyin, ati ìja nyin? 13 Ẹ mú awọn ọkunrin ọlọgbọ́n wá, ati amoye, ati ẹniti a mọ̀ ninu awọn ẹ̀ya nyin, emi o si fi wọn jẹ olori nyin. 14 Ẹnyin si da mi li ohùn, ẹ si wipe, Ohun ti iwọ sọ nì, o dara lati ṣe. 15 Bẹ̃ni mo mú olori awọn ẹ̀ya nyin, awọn ọlọgbọ́n ọkunrin, ẹniti a mọ̀, mo si fi wọn jẹ olori nyin, olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwa-mẹwa, ati awọn olori gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya nyin. 16 Mo si fi aṣẹ lelẹ fun awọn onidajọ nyin nigbana pe, Ẹ ma gbọ́ ẹjọ́ lãrin awọn arakunrin nyin, ki ẹ si ma ṣe idajọ ododo lãrin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati alejò ti mbẹ lọdọ rẹ̀. 17 Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju ni idajọ; ẹ gbọ́ ti ewe gẹgẹ bi ti àgba; ẹ kò gbọdọ bẹ̀ru oju enia; nitoripe ti Ọlọrun ni idajọ: ọ̀ran ti o ba si ṣoro fun nyin, ẹ mú u tọ̀ mi wá, emi o si gbọ́ ọ. 18 Emi si fi aṣẹ ohun gbogbo ti ẹnyin o ma ṣe lelẹ fun nyin ni ìgba na.

Mose Rán Àwọn Amí láti Kadeṣi Banea Lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí

19 Nigbati awa si kuro ni Horebu, awa rìn gbogbo aginjù nla nì ti o ni ẹ̀ru já, ti ẹnyin ri li ọ̀na òke awọn ọmọ Amori, bi OLUWA Ọlọrun wa ti fun wa li aṣẹ; awa si wá si Kadeṣi-barnea. 20 Emi si wi fun nyin pe, Ẹnyin dé òke awọn ọmọ Amori na, ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa. 21 Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ. 22 Gbogbo nyin si tọ̀ mi wá, ẹ si wipe, Jẹ ki awa ki o rán enia lọ siwaju wa, ki nwọn ki o si rìn ilẹ na wò fun wa, ki nwọn ki o si mú ìhin pada tọ̀ wa wá, niti ọ̀na ti a o ba gòke lọ, ati ti ilu ti a o yọ si. 23 Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si yàn ọkunrin mejila ninu nyin, ẹnikan ninu ẹ̀ya kan: 24 Nwọn si yipada nwọn si lọ sori òke, nwọn si wá si afonifoji Eṣkolù, nwọn si rìn ilẹ na wò. 25 Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ wá fun wa, nwọn si mú ìhin pada wá fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ ti OLUWA wa fi fun wa, ilẹ rere ni. 26 Ṣugbọn ẹnyin kò fẹ́ gòke lọ, ẹnyin si ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin: 27 Ẹnyin si kùn ninu agọ́ nyin, wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa lati Egipti jade wá, lati fi wa lé ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati run wa. 28 Nibo li awa o gbé gòke lọ? awọn arakunrin wa ti daiyajá wa, wipe, Awọn enia na sigbọnlẹ jù wa lọ; ilu wọn tobi a si mọdi wọn kan ọrun; pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀. 29 Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. 30 OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin; 31 Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi. 32 Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́. 33 Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán.

OLUWA Jẹ Àwọn Ọmọ Israẹli Níyà

34 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe, 35 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin, 36 Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata. 37 OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀: 38 Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i. 39 Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i. 40 Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ẹ pada, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa. 41 Nigbana li ẹ dahùn, ẹ si wi fun mi pe, Awa ti ṣẹ̀ si OLUWA, awa o gòke lọ, a o si jà, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa palaṣẹ fun wa. Ati olukuluku nyin dì ihamọra ogun rẹ̀, ẹnyin mura lati gùn ori òke na. 42 OLUWA si wi fun mi pe, Wi fun wọn pe, Ẹ máṣe gòke lọ, bẹ̃ni ki ẹ màṣe jà; nitoriti emi kò sí lãrin nyin; ki a má ba lé nyin niwaju awọn ọtá nyin. 43 Mo sọ fun nyin, ẹnyin kò si gbọ́; ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA, ẹnyin sì kùgbu lọ si ori òke na. 44 Awọn ọmọ Amori, ti ngbé ori òke na, si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, bi oyin ti iṣe, nwọn si run nyin ni Seiri, titi dé Horma. 45 Ẹnyin si pada ẹ sì sọkun niwaju OLUWA; ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ ohùn nyin, bẹ̃ni kò fetisi nyin.

Àkókò Tí Àwọn Ọmọ Israẹli Fi Wà ninu Aṣálẹ̀

46 Ẹnyin si joko ni Kadeṣi li ọjọ́ pupọ̀, gẹgẹ bi ọjọ́ ti ẹnyin joko nibẹ̀.

Deuteronomi 2

1 NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀. 2 OLUWA si sọ fun mi pe, 3 Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa. 4 Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi: 5 Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní. 6 Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu. 7 Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ. 8 Nigbati awa si kọja lẹba awọn arakunrin wa awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, li ọ̀na pẹtẹlẹ̀ lati Elati wá, ati lati Esion-geberi wá, awa pada, awa si kọja li ọ̀na aginjù Moabu. 9 OLUWA si wi fun mi pe, Ẹ máṣe bi awọn ara Moabu ninu, bẹ̃ni ki ẹ máṣe fi ogun jà wọn: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ rẹ̀ fun ọ ni iní; nitoriti mo ti fi Ari fun awọn ọmọ Lotu ni iní. 10 (Awọn Emimu ti ngbé inu rẹ̀ ni ìgba atijọ rí, awọn enia nla, nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki: 11 Ti a nkà kún awọn omirán, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn awọn ara Moabu a ma pè wọn ni Emimu. 12 Awọn ọmọ Hori pẹlu ti ngbé Seiri rí, ṣugbọn awọn ọmọ Esau tẹle wọn, nwọn si run wọn kuro niwaju wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; gẹgẹ bi Israeli ti ṣe si ilẹ-iní rẹ̀, ti OLUWA fi fun wọn.) 13 Mo ní, Dide nisisiyi, ki ẹ si gòke odò Seredi. Awa si gòke odò Seredi lọ. 14 Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn. 15 Pẹlupẹlu ọwọ́ OLUWA lodi si wọn nitõtọ, lati run wọn kuro ninu ibudó, titi nwọn fi run tán. 16 Bẹ̃li o si ṣe, ti gbogbo awọn ologun nì run, ti nwọn si kú tán ninu awọn enia na, 17 OLUWA si sọ fun mi pe, 18 Iwọ o là ilẹ Ari lọ li oni, li àgbegbe Moabu: 19 Nigbati iwọ ba sunmọtosi awọn ọmọ Ammoni, máṣe bi wọn ninu, bẹ̃ni ki o máṣe bá wọn jà: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ awọn ọmọ Ammoni fun ọ ni iní: nitoriti mo ti fi i fun awọn ọmọ Lotu ni iní. 20 (A si kà eyinì pẹlu si ilẹ awọn omirán; awọn omirán ti ngbé inu rẹ̀ rí; awọn ọmọ Ammoni a si ma pè wọn ni Samsummimu. 21 Awọn enia nla, ti nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn OLUWA run wọn niwaju wọn; nwọn si tẹle wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; 22 Bi o ti ṣe fun awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, nigbati o run awọn ọmọ Hori kuro niwaju wọn; ti nwọn si tẹle wọn, ti nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn titi di oni-oloni: 23 Ati awọn ọmọ Affimu ti ngbé awọn ileto, titi dé Gasa, awọn ọmọ Kaftori, ti o ti ọdọ Kaftori wá, run wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn.) 24 Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun. 25 Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi fi ìfoya rẹ, ati ẹ̀ru rẹ sara awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si warìri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ.

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Sihoni Ọba

26 Mo si rán onṣẹ lati aginjù Kedemotu lọ sọdọ Sihoni ọba Heṣboni pẹlu ọ̀rọ alafia, wipe, 27 Jẹ ki emi ki o là ilẹ rẹ kọja lọ: ọ̀na opópo li emi o gbà, emi ki yio yà si ọtún tabi si òsi. 28 Pẹlu owo ni ki iwọ ki o tà onjẹ fun mi, ki emi ki o jẹ; pẹlu owo ni ki iwọ ki o si fun mi li omi, ki emi ki o mu: kìki ki nsá fi ẹsẹ̀ mi kọja; 29 Bi awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri, ati awọn ara Moabu ti ngbé Ari, ti ṣe si mi; titi emi o fi gòke Jordani si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa. 30 Ṣugbọn Sihoni ọba Heṣboni kò jẹ ki a kọja lẹba on: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u li àiya le, o sọ ọkàn rẹ̀ di agídi, ki o le fi on lé ọ lọwọ, bi o ti ri li oni yi. 31 OLUWA si sọ fun mi pe, Wò o, emi ti bẹ̀rẹsi fi Sihoni ati ilẹ rẹ̀ fun ọ niwaju rẹ: bẹ̀rẹsi gbà a, ki iwọ ki o le ní ilẹ rẹ̀. 32 Nigbana ni Sihoni jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Jahasi. 33 OLUWA Ọlọrun si fi i lé wa lọwọ niwaju wa; awa si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀. 34 Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na, awa si run awọn ọkunrin patapata, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ, ni gbogbo ilu; awa kò jẹ ki ọkan ki o kù: 35 Kìki ohunọ̀sin li a kó ni ikogun fun ara wa, ati ikogun ilu wọnni ti awa kó. 36 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati lati ilu ni lọ ti mbẹ lẹba afonifoji nì, ani dé Gileadi, kò sí ilu kan ti o le jù fun wa: OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn fun wa: 37 Kìki ilẹ awọn ọmọ Ammoni ni iwọ kò sunmọ, tabi ibikibi lẹba odò Jaboku, tabi ilu òke wọnni, tabi ibikibi ti OLUWA Ọlọrun wa kọ̀ fun wa.

Deuteronomi 3

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Ogu Ọba

1 NIGBANA li awa pada, a si lọ soke li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Edrei. 2 OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni. 3 Bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun wa fi Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, lé wa lọwọ pẹlu: awa si kọlù u titi kò si kù ẹnikan silẹ fun u. 4 Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na; kò sí ilu kan ti awa kò gbà lọwọ wọn; ọgọta ilu, gbogbo ẹkùn Argobu, ilẹ ọba Ogu ni Baṣani. 5 Gbogbo ilu wọnyi li a mọ odi giga si pẹlu ibode, ati idabu-ẹ̀kun; laikà ọ̀pọlọpọ ilu alailodi. 6 Awa si run wọn patapata, bi awa ti ṣe si Sihoni ọba Heṣboni, ni rirun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ patapata, ni ilu na gbogbo. 7 Ṣugbọn gbogbo ohunọ̀sin, ati ikogun ilu wọnni li awa kó ni ikogun fun ara wa. 8 Nigbana li awa gbà li ọwọ́ awọn ọba ọmọ Amori mejeji, ilẹ ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani, lati afonifoji Arnoni lọ dé òke Hermoni; 9 (Awọn ara Sidoni a ma pè Hermoni ni Sirioni, ati awọn ọmọ Amori a si ma pè e ni Seniri;) 10 Gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo Gileadi, ati gbogbo Baṣani, dé Saleka ati Edrei, awọn ilu ilẹ ọba Ogu ni Baṣani. 11 (Ogu ọba Baṣani nikanṣoṣo li o sá kù ninu awọn omirán iyokù; kiyesi i, akete rẹ̀ jẹ́ akete irin; kò ha wà ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni? igbọnwọ mẹsan ni gigùn rẹ̀, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ni igbọnwọ ọkunrin.)

Àwọn Ẹ̀yà Tí Wọ́n Tẹ̀dó sí Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

12 Ati ilẹ na yi, ti awa gbà ni ìgbana, lati Aroeri, ti mbẹ lẹba afonifoji Arnoni, ati àbọ òke Gileadi, ati ilu inu rẹ̀, ni mo fi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi: 13 Ati iyokù Gileadi, ati gbogbo Baṣani, ilẹ ọba Ogu, ni mo fi fun àbọ ẹ̀ya Manasse; gbogbo ẹkùn Argobu, pẹlu gbogbo Baṣani. (Ti a ma pè ni ilẹ awọn omirán. 14 Jairi ọmọ Manasse mú gbogbo ilẹ Argobu, dé opinlẹ Geṣuri ati Maakati; o si sọ wọn, ani Baṣan, li orukọ ara rẹ̀, ni Haffotu-jairi titi, di oni.) 15 Mo si fi Gileadi fun Makiri. 16 Ati awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi ni mo fi fun lati Gileadi, ani dé afonifoji Arnoni, agbedemeji afonifoji, ati opinlẹ rẹ̀; ani dé odò Jaboku, ti iṣe ipinlẹ awọn ọmọ Ammoni; 17 Pẹtẹlẹ̀ ni pẹlu, ati Jordani ati opinlẹ rẹ̀, lati Kinnereti lọ titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, nisalẹ awọn orisun Pisga ni ìha ìla-õrùn. 18 Mo si fun nyin li aṣẹ ni ìgbana, wipe, OLUWA Ọlọrun nyin ti fi ilẹ yi fun nyin lati ní i: ẹnyin o si kọja si ìha keji ni ihamọra ogun niwaju awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn akọni ọkunrin. 19 Kìki awọn aya nyin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, (emi mọ̀ pe ẹnyin lí ohunọ̀sin pupọ̀,) ni yio duro ni ilu nyin ti mo ti fi fun nyin; 20 Titi OLUWA o fi fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti fi fun ẹnyin, ati titi awọn pẹlu yio fi ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun wọn loke Jordani: nigbana li ẹnyin o pada, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ti mo ti fi fun nyin. 21 Emi si fi aṣẹ fun Joṣua ni ìgbana, wipe, Oju rẹ ti ri gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si awọn ọba mejeji wọnyi: bẹ̃ni OLUWA yio ṣe si gbogbo ilẹ-ọba nibiti iwọ o kọja. 22 Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio jà fun nyin.

Ọlọrun Kò Jẹ́ kí Mose Wọ Ilẹ̀ Kenaani

23 Emi si bẹ̀ OLUWA ni ìgba na, wipe, 24 OLUWA Ọlọrun, iwọ ti bẹ̀rẹsi fi titobi rẹ hàn fun iranṣẹ rẹ, ati ọwọ́ agbara rẹ: nitoripe Ọlọrun wo ni li ọrun ati li aiye, ti o le ṣe gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi iṣẹ-agbara rẹ? 25 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja si ìha keji, ki emi si ri ilẹ rere na ti mbẹ loke Jordani, òke daradara nì, ati Lebanoni. 26 Ṣugbọn OLUWA binu si mi nitori nyin, kò si gbọ́ ti emi: OLUWA si wi fun mi pe, O to gẹ; má tun bá mi sọ ọ̀rọ yi mọ́. 27 Gùn ori òke Pisga lọ, ki o si gbé oju rẹ soke si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù, ati si ìha ìla-õrùn, ki o si fi oju rẹ wò o: nitoripe iwọ ki yio gòke Jordani yi. 28 Ṣugbọn fi aṣẹ fun Joṣua, ki o si gbà a niyanju, ki o si mu u li ọkàn le: nitoripe on ni yio gòke lọ niwaju awọn enia yi, on o si mu wọn ni ilẹ na ti iwọ o ri. 29 Awa si joko li afonifoji ti o kọjusi Beti-peori.

Deuteronomi 4

Mose Rọ Àwọn Ọmọ Israẹli Pé kí Wọn Máa Gbọ́ràn

1 NJẸ nisisiyi Israeli, fetisi ìlana ati idajọ, ti emi nkọ́ nyin, lati ṣe wọn; ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ si lọ igba ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin fi fun nyin. 2 Ẹ kò gbọdọ fikún ọ̀rọ na ti mo palaṣẹ fun nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀, ki ẹnyin ki o le pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin. 3 Oju nyin ti ri ohun ti OLUWA ṣe nitori Baali-peori: nitoripe gbogbo awọn ọkunrin ti o tẹlé Baali-peori lẹhin, OLUWA Ọlọrun rẹ ti run wọn kuro lãrin rẹ. 4 Ṣugbọn ẹnyin ti o faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gbogbo nyin mbẹ lãye li oni. 5 Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a. 6 Nitorina ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; nitoripe eyi li ọgbọ́n nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ́ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọ́n ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi. 7 Nitori orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si? 8 Ati orilẹ-ède nla wo li o si wà, ti o ní ìlana ati idajọ ti iṣe ododo to bi gbogbo ofin yi, ti mo fi siwaju nyin li oni? 9 Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ; 10 Li ọjọ́ ti iwọ duro niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu, nigbati OLUWA wi fun mi pe, Pe awọn enia yi jọ fun mi, emi o si mu wọn gbọ́ ọ̀rọ mi, ki nwọn ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru mi li ọjọ́ gbogbo ti nwọn o wà lori ilẹ, ati ki nwọn ki o le ma kọ́ awọn ọmọ wọn. 11 Ẹnyin si sunmọtosi, ẹ si duro nisalẹ òke nì; òke na si njòna dé agbedemeji ọrun, pẹlu òkunkun, ati awọsanma, ati òkunkun biribiri. 12 OLUWA si sọ̀rọ si nyin lati ãrin iná na wá: ẹnyin gbọ́ ohùn ọ̀rọ na, ṣugbọn ẹ kò ri apẹrẹ kan; kìki ohùn li ẹnyin gbọ́. 13 O si sọ majẹmu rẹ̀ fun nyin, ti o palaṣẹ fun nyin lati ṣe, ani ofin mẹwa nì; o si kọ wọn sara walã okuta meji. 14 OLUWA si paṣẹ fun mi ni ìgba na lati kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.

Ìkìlọ̀ nípa Ìbọ̀rìṣà

15 Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá: 16 Ki ẹnyin ki o má ba bà ara nyin jẹ́, ki ẹ má si lọ ṣe ere gbigbẹ, apẹrẹ ohunkohun, aworán akọ tabi abo. 17 Aworán ẹrankẹran ti mbẹ lori ilẹ, aworán ẹiyẹkẹiyẹ ti nfò li oju-ọrun. 18 Aworán ohunkohun ti nrakò lori ilẹ, aworán ẹjakẹja ti mbẹ ninu omi nisalẹ ilẹ: 19 Ati ki iwọ ki o má ba gbé oju rẹ soke ọrun, nigbati iwọ ba si ri õrùn, ati oṣupa, ati irawọ, ani gbogbo ogun ọrun, ki a má ba sún ọ lọ ibọ wọn, ki o si ma sìn wọn, eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun gbogbo orilẹ-ède labẹ ọrun gbogbo. 20 Ṣugbọn OLUWA ti gbà nyin, o si mú nyin lati ileru irin, lati Egipti jade wá, lati ma jẹ́ enia iní fun u, bi ẹnyin ti ri li oni yi. 21 OLUWA si binu si mi nitori nyin, o si bura pe, emi ki yio gòke Jordani, ati pe emi ki yio wọ̀ inu ilẹ rere nì, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni ilẹ-iní. 22 Ṣugbọn emi o kú ni ilẹ yi, emi ki yio gòke odò Jordani: ṣugbọn ẹnyin o gòke ẹnyin o si gbà ilẹ rere na. 23 Ẹ ma ṣọra nyin, ki ẹnyin má ba gbagbé majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti o ti bá nyin dá, ki ẹnyin má ba lọ ṣe ere finfin fun ara nyin, tabi aworán ohunkohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti kọ̀ fun ọ. 24 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú. 25 Nigbati iwọ ba bi ọmọ, ati ọmọ ọmọ, ti ẹ ba si pẹ ni ilẹ na, ti ẹ si bà ara nyin jẹ́, ti ẹ si ṣe ere finfin, tabi aworán ohunkohun, ti ẹ si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA Ọlọrun rẹ lati mu u binu: 26 Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata. 27 OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si. 28 Nibẹ̀ li ẹnyin o si ma sìn oriṣa, iṣẹ ọwọ́ enia, igi ati okuta, ti kò riran, ti kò si gbọran, ti kò jẹun, ti kò si gbõrun. 29 Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a. 30 Nigbati iwọ ba mbẹ ninu ipọnju, ti nkan gbogbo wọnyi ba si bá ọ, nikẹhin ọjọ́, bi iwọ ba yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́: 31 Nitoripe Ọlọrun alãnu ni OLUWA Ọlọrun rẹ; on ki yio kọ̀ ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio run ọ, bẹ̃ni ki yio gbagbé majẹmu awọn baba rẹ, ti o ti bura fun wọn. 32 Njẹ bère nisisiyi niti ọjọ́ igbãni, ti o ti mbẹ ṣaju rẹ, lati ọjọ́ ti Ọlọrun ti dá enia sori ilẹ, ki o si bère lati ìha ọrun kini dé ìha keji, bi irú nkan bi ohun nla yi wà rí, tabi bi a gburó irú rẹ̀ rí? 33 Awọn enia kan ha gbọ́ ohùn Ọlọrun rí ki o ma bá wọn sọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi iwọ ti gbọ́, ti o si wà lãye? 34 Tabi Ọlọrun ha dán a wò rí lati lọ mú orilẹ-ède kan fun ara rẹ̀ lati ãrin orilẹ-ède miran wá, nipa idanwò, nipa àmi, ati nipa iṣẹ-iyanu, ati nipa ogun, ati nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa, ati nipa ẹ̀ru nla, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ṣe fun nyin ni Egipti ni oju nyin? 35 Iwọ li a fihàn, ki iwọ ki o le mọ̀ pe OLUWA on li Ọlọrun; kò sí ẹlomiran lẹhin rẹ̀. 36 O mu ọ gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ọrun wá, ki o le kọ́ ọ: ati lori ilẹ aiye o fi iná nla rẹ̀ hàn ọ; iwọ si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ lati ãrin iná wá. 37 Ati nitoriti o fẹ́ awọn baba rẹ, nitorina li o ṣe yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, o si fi agbara nla rẹ̀ mú ọ lati Egipti jade wá li oju rẹ̀; 38 Lati lé awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju rẹ, ti o tobi, ti o si lagbara jù ọ lọ, lati mú ọ wọle, lati fi ilẹ wọn fun ọ ni iní, bi o ti ri li oni yi. 39 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ li oni, ki o si rò li ọkàn rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: kò sí ẹlomiran. 40 Nitorina ki iwọ ki o pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati ofin rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ lori ilẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lailai.

Àwọn Ìlú Ààbò Tí Ó Wà ní Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

41 Nigbana ni Mose yà ilu mẹta sọ̀tọ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn. 42 Ki apania ki o le ma sá sibẹ̀, ti o ba ṣì ẹnikeji rẹ̀ pa, ti kò si korira rẹ̀ ni ìgba atijọ rí; ati pe bi o ba sá si ọkan ninu ilu wọnyi ki o le là: 43 Beseri ni ijù, ni ilẹ pẹtẹlẹ̀, ti awọn ọmọ Reubeni; ati Ramotu ni Gileadi, ti awọn ọmọ Gadi; ati Golani ni Baṣani, ti awọn ọmọ Manasse.

Àlàyé lórí Òfin Ọlọrun Tí Mose Fẹ́ fún Wọn

44 Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli: 45 Wọnyi li ẹrí, ati ìlana, ati idajọ, ti Mose filelẹ fun awọn ọmọ Israeli, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá; 46 Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá: 47 Nwọn si gbà ilẹ rẹ̀, ati ilẹ Ogu ọba Baṣani, awọn ọba Amori mejeji ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn; 48 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,) 49 Ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ nì, ni ìha ẹ̀bá Jordani ni ìha ìla-õrùn, ani dé okun pẹtẹlẹ̀ nì, nisalẹ awọn orisun Pisga.

Deuteronomi 5

Òfin Mẹ́wàá

1 MOSE si pè gbogbo Israeli, o si wi fun wọn pe, Israeli, gbọ́ ìlana ati idajọ ti emi nsọ li etí nyin li oni, ki ẹnyin ki o le kọ́ wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ́, lati ma ṣe wọn. 2 OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu ni Horebu. 3 OLUWA kò bá awọn baba wa dá majẹmu yi, bikoṣe awa, ani awa, ti gbogbo wa mbẹ lãye nihin li oni. 4 OLUWA bá nyin sọ̀rọ li ojukoju lori òke na, lati ãrin iná wá, 5 (Emi duro li agbedemeji OLUWA ati ẹnyin ni ìgba na, lati sọ ọ̀rọ OLUWA fun nyin: nitoripe ẹnyin bẹ̀ru nitori iná na, ẹnyin kò si gòke lọ sori òke na;) wipe, 6 Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. 7 Iwọ kò gbọdọ ní ọlọrun miran pẹlu mi. 8 Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworán apẹrẹ kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti mbẹ ni ilẹ nisalẹ, tabi ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ: 9 Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitoripe emi OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara iran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi. 10 Emi a si ma ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si pa ofin mi mọ́. 11 Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ li asan: nitoriti OLUWA ki yio mu ẹniti o pè orukọ rẹ̀ li asan bi alailẹṣẹ lọrùn. 12 Kiyesi ọjọ́-isimi lati yà a simimọ́, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ. 13 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: 14 Ṣugbọn ọjọ́ keje li ọjọ́-isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ, ati ohunọ̀sin rẹ kan, ati alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ; ki ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ki o le simi gẹgẹ bi iwọ. 15 Si ranti pe iwọ ti ṣe iranṣẹ ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ibẹ̀ jade wá nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa: nitorina li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe paṣẹ fun ọ lati pa ọjọ́-isimi mọ́. 16 Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ, ati ki o le dara fun ọ, ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 17 Iwọ kò gbọdọ pania. 18 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. 19 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jale. 20 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹri-eké si ẹnikeji rẹ. 21 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, oko rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ. 22 Ọ̀rọ wọnyi ni OLUWA sọ fun gbogbo ijọ nyin lori òke lati ãrin iná, awọsanma, ati lati inu òkunkun biribiri wá, pẹlu ohùn nla: kò si fi kún u mọ́. O si kọ wọn sara walã okuta meji, o si fi wọn fun mi.

Ẹ̀rù Ba Àwọn Ọmọ Israẹli

23 O si ṣe, nigbati ẹnyin gbọ́ ohùn nì lati ãrin òkunkun na wá, ti òke na si njó, ti ẹnyin sunmọ ọdọ mi, gbogbo olori awọn ẹ̀ya nyin, ati awọn àgba nyin: 24 Ẹnyin si wipe, Kiyesi i, OLUWA Ọlọrun wa fi ogo rẹ̀ ati titobi rẹ̀ hàn wa, awa si ti gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ãrin iná wá: awa ti ri li oni pe, OLUWA a ma ba enia sọ̀rọ̀, on a si wà lãye. 25 Njẹ nisisiyi ẽṣe ti awa o fi kú? nitoripe iná nla yi yio jó wa run: bi awa ba tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa, njẹ awa o kú. 26 Nitoripe tani mbẹ ninu gbogbo araiye ti o ti igbọ́ ohùn Ọlọrun alãye ti nsọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi awa ti gbọ́, ti o si wà lãye? 27 Iwọ sunmọtosi, ki o si gbọ́ gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa yio wi: ki iwọ ki o sọ fun wa gbogbo ohun ti OLUWA Ọlọrun wa yio sọ fun ọ: awa o si gbọ́, awa o si ṣe e. 28 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin sọ fun mi; OLUWA si sọ fun mi pe, emi ti gbọ́ ohùn ọ̀rọ awọn enia yi, ti nwọn sọ fun ọ: nwọn wi rere ni gbogbo eyiti nwọn sọ. 29 Irú ọkàn bayi iba ma wà ninu wọn, ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru mi, ki nwọn ki o si le ma pa gbogbo ofin mi mọ́ nigbagbogbo, ki o le dara fun wọn, ati fun awọn ọmọ wọn titilai! 30 Lọ wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ sinu agọ́ nyin. 31 Ṣugbọn, iwọ, duro nihin lọdọ mi, emi o si sọ ofin nì gbogbo fun ọ, ati ìlana, ati idajọ, ti iwọ o ma kọ́ wọn, ki nwọn ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na ti mo ti fi fun wọn lati ní. 32 Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesi ati ṣe bi OLUWA Ọlọrun nyin ti paṣẹ fun nyin: ki ẹnyin ki o máṣe yi si ọtún tabi si òsi. 33 Ki ẹnyin ki o si ma rìn ninu gbogbo ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun nyin palaṣẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki o si le dara fun nyin, ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ ti ẹnyin yio ní.

Deuteronomi 6

Òfin Ńlá

1 NJẸ wọnyi li ofin, ìlana, ati idajọ, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti palaṣẹ lati ma kọ́ nyin, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ nibiti ẹnyin gbé nlọ lati gbà a: 2 Ki iwọ ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ìlana rẹ̀ ati ofin rẹ̀ mọ́, ti emi fi fun ọ, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ. 3 Nitorina gbọ́, Israeli, ki o si ma kiyesi i lati ṣe e; ki o le dara fun ọ, ati ki ẹnyin ki o le ma pọ̀si i li ọ̀pọlọpọ, bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti ṣe ileri fun ọ, ni ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 4 Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni. 5 Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ. 6 Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ: 7 Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide. 8 Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ. 9 Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọ̀na-ode rẹ.

Ìkìlọ̀ nípa Ìwà Àìgbọràn

10 Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, ti o bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fun ọ ni ilu ti o tobi ti o si dara, ti iwọ kò mọ̀, 11 Ati ile ti o kún fun ohun rere gbogbo, ti iwọ kò kún, ati kanga wiwà, ti iwọ kò wà, ọgbà-àjara ati igi oróro, ti iwọ kò gbìn; nigbati iwọ ba jẹ tán ti o ba si yó; 12 Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú. 13 Bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma sìn i, ki o si ma bura li orukọ rẹ̀. 14 Ẹnyin kò gbọdọ tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia, ti o yi nyin ká kiri; 15 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni ninu nyin; ki ibinu OLUWA Ọlọrun rẹ ki o má ba rú si ọ, on a si run ọ kuro lori ilẹ. 16 Ẹnyin kò gbọdọ dán OLUWA Ọlọrun nyin wò, bi ẹnyin ti dan a wò ni Massa. 17 Ki ẹnyin ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́ gidigidi, ati ẹrí rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ti o filelẹ li aṣẹ fun ọ. 18 Ki iwọ ki o ma ṣe eyiti o tọ́, ti o si dara li oju OLUWA: ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wọ̀ ilẹ rere nì lọ ki o si gbà a, eyiti OLUWA bura fun awọn baba rẹ, 19 Lati tì awọn ọtá rẹ gbogbo jade kuro niwaju rẹ, bi OLUWA ti wi. 20 Nigbati ọmọ rẹ ba bi ọ lère lẹhin-ọla, wipe, Kini èredi ẹrí, ati ìlana, ati idajọ wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun filelẹ li aṣẹ fun nyin? 21 Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá. 22 OLUWA si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ti o tobi ti o si buru hàn lara Egipti, lara Farao, ati lara gbogbo ara ile rẹ̀ li oju wa: 23 O si mú wa jade lati ibẹ̀ wá, ki o le mú wa wọ̀ inu rẹ̀, lati fun wa ni ilẹ na ti o bura fun awọn baba wa. 24 OLUWA si pa a laṣẹ fun wa, lati ma ṣe gbogbo ìlana wọnyi, lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun wa, fun ire wa nigbagbogbo, ki o le pa wa mọ́ lãye, bi o ti ri li oni yi. 25 Yio si jẹ́ ododo wa, bi awa ba nṣọ́ ati ma ṣe gbogbo ofin wọnyi niwaju OLUWA Ọlọrun wa, bi o ti paṣẹ fun wa.

Deuteronomi 7

Àwọn Eniyan OLUWA

1 NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ; 2 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si kọlù wọn; ki o si run wọn patapata; iwọ kò gbọdọ bá wọn dá majẹmu, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: 3 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá wọn dá ana; ọmọbinrin rẹ ni iwọ kò gbọdọ fi fun ọmọkunrin rẹ̀, ati ọmọbinrin rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ mú fun ọmọkunrin rẹ. 4 Nitoripe nwọn o yi ọmọkunrin rẹ pada lati ma tọ̀ mi lẹhin, ki nwọn ki o le ma sìn ọlọrun miran: ibinu OLUWA o si rú si nyin, on a si run ọ lojiji. 5 Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bì ọwọ̀n wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn. 6 Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ. 7 OLUWA kò fi ifẹ́ rẹ̀ si nyin lara, bẹ̃ni kò yàn nyin, nitoriti ẹnyin pọ̀ ni iye jù awọn enia kan lọ; nitoripe ẹnyin li o tilẹ kére jù ninu gbogbo enia: 8 Ṣugbọn nitoriti OLUWA fẹ́ nyin, ati nitoriti on fẹ́ pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mọ́, ni OLUWA ṣe fi ọwọ́ agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwọ́ Farao ọba Egipti. 9 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran; 10 Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀. 11 Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.

Ibukun Tí Ó Wà ninu Ìgbọràn

12 Yio si ṣe, nitoriti ẹnyin fetisi idajọ wọnyi, ti ẹ si npa wọn mọ́, ti ẹ si nṣe wọn, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio ma pa majẹmu ati ãnu mọ́ fun ọ, ti o ti bura fun awọn baba rẹ: 13 On o si fẹ́ ọ, yio si bukún ọ, yio si mu ọ bisi i: on o si bukún ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ, ibisi malu rẹ, ati awọn ọmọ agbo-agutan rẹ, ni ilẹ na ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ. 14 Iwọ o jẹ́ ẹni ibukún jù gbogbo enia lọ: ki yio sí akọ tabi abo ninu nyin ti yio yàgan, tabi ninu ohunọ̀sin nyin. 15 OLUWA yio si gbà àrun gbogbo kuro lọdọ rẹ, ki yio si fi ọkan ninu àrun buburu Egipti, ti iwọ mọ̀, si ọ lara, ṣugbọn on o fi wọn lé ara gbogbo awọn ti o korira rẹ. 16 Iwọ o si run gbogbo awọn enia ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi fun ọ; oju rẹ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn awọn oriṣa wọn; nitoripe idẹkùn li eyinì yio jẹ́ fun ọ. 17 Bi iwọ ba wi li ọkàn rẹ pe, Awọn orilẹ-ède wọnyi pọ̀ jù mi lọ; bawo li emi o ṣe le lé wọn jade? 18 Ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru wọn: ṣugbọn ki iwọ ki o ranti daradara ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Farao, ati si gbogbo Egipti; 19 Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà. 20 Pẹlupẹlu OLUWA Ọlọrun rẹ yio rán agbọ́n sinu wọn, titi awọn ti o kù, ti nwọn si fi ara wọn pamọ́ fun ọ yio fi run. 21 Ki iwọ ki o máṣe fòya wọn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lãrin rẹ, Ọlọrun ti o tobi ti o si lẹrù. 22 OLUWA Ọlọrun rẹ yio tì awọn orilẹ-ède na jade diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ki o máṣe run wọn tán lẹ̃kan, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba pọ̀ si ọ. 23 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi wọn lé ọ lọwọ, yio si fi iparun nla pa wọn run, titi nwọn o fi run. 24 On o si fi awọn ọba wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si pa orukọ wọn run kuro labẹ ọrun: kò sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ, titi iwọ o fi run wọn tán. 25 Ere finfin oriṣa wọn ni ki ẹnyin ki o fi iná jó: iwọ kò gbọdọ ṣe ojukokoro fadakà tabi wurà ti mbẹ lara wọn, bẹ̃ni ki o máṣe mú u fun ara rẹ, ki o má ba di idẹkùn fun ọ; nitoripe ohun irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ: 26 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ mú ohun irira wá sinu ile rẹ, ki iwọ ki o má ba di ẹni ifibú bi rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o korira rẹ̀ patapata, ki iwọ ki o si kà a si ohun irira patapata; nitoripe ohun ìyasọtọ ni.

Deuteronomi 8

Ilẹ̀ Tí Ó Dára fún Ìní

1 GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin. 2 Ki iwọ ki o si ranti ọ̀na gbogbo ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti mu ọ rìn li aginjù lati ogoji ọdún yi wá, lati rẹ̀ ọ silẹ, ati lati dan ọ wò, lati mọ̀ ohun ti o wà li àiya rẹ, bi iwọ o pa ofin rẹ̀ mọ́, bi bẹ̃kọ. 3 O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye. 4 Aṣọ rẹ kò gbó mọ́ ọ lara, bẹ̃li ẹsẹ̀ rẹ kò wú, lati ogoji ọdún yi wá. 5 Ki iwọ ki o si mọ̀ li ọkàn rẹ pe, bi enia ti ibá ọmọ rẹ̀ wi, bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wi. 6 Ki iwọ ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma bẹ̀ru rẹ̀. 7 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji ati òke jade wa; 8 Ilẹ alikama ati ọkà-barle, ati àjara ati igi ọpọtọ ati igi pomegranate; ilẹ oróro olifi, ati oyin; 9 Ilẹ ninu eyiti iwọ ki o fi ìṣẹ jẹ onjẹ, iwọ ki yio fẹ ohun kan kù ninu rẹ̀; ilẹ ti okuta rẹ̀ iṣe irin, ati lati inu òke eyiti iwọ o ma wà idẹ. 10 Nigbati iwọ ba si jẹun tán ti o si yo, nigbana ni iwọ o fi ibukún fun OLUWA Ọlọrun rẹ, nitori ilẹ rere na ti o fi fun ọ.

Ìkìlọ̀ nípa Gbígbàgbé OLUWA

11 Ma kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ṣe gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, li aipa ofin rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni: 12 Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rẹ̀; 13 Ati ki ọwọ́-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ̀si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọ̀si i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ní pọ̀si i; 14 Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú; 15 Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá; 16 Ẹniti o fi manna bọ́ ọ li aginjù, ti awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; ki o le rẹ̀ ọ silẹ, ki o le dan ọ wò, lati ṣe ọ li ore nigbẹhin rẹ: 17 Iwọ a si wi li ọkàn rẹ pe, Agbara mi ati ipa ọwọ́ mi li o fun mi li ọrọ̀ yi. 18 Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati lí ọrọ̀, ki on ki o le fi idi majẹmu rẹ̀ ti o bura fun awọn baba rẹ kalẹ, bi o ti ri li oni yi. 19 Yio si ṣe, bi iwọ ba gbagbe OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ si tẹle ọlọrun miran, ti o si nsìn wọn, ti o si mbọ wọn, emi tẹnumọ́ ọ fun nyin pe, rirun li ẹnyin o run. 20 Bi awọn orilẹ-ède ti OLUWA run kuro niwaju nyin, bẹ̃li ẹnyin o run; nitoripe ẹnyin ṣe àigbọran si ohùn OLUWA Ọlọrun nyin.

Deuteronomi 9

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣe Àìgbọràn

1 GBỌ́, Israeli: iwọ o gòke Jordani li oni, lati wọle lọ ìgba awọn orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù ọ lọ, ilu ti o tobi, ti a mọdi rẹ̀ kàn ọrun, 2 Awọn enia ti o tobi ti o si sigbọnlẹ, awọn ọmọ Anaki, ti iwọ mọ̀, ti iwọ si gburó pe, Tali o le duro niwaju awọn ọmọ Anaki? 3 Iwọ o si mọ̀ li oni pe, OLUWA Ọlọrun rẹ on ni ngòke ṣaju rẹ lọ bi iná ajonirun; yio pa wọn run, on o si rẹ̀ wọn silẹ niwaju rẹ: iwọ o si lé wọn jade, iwọ o si pa wọn run kánkán, bi OLUWA ti wi fun ọ. 4 Máṣe sọ li ọkàn rẹ, lẹhin igbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba tì wọn jade kuro niwaju rẹ, wipe, Nitori ododo mi ni OLUWA ṣe mú mi wá lati gbà ilẹ yi: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ. 5 Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọ̀rọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu. 6 Nitorina ki o yé ọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ kò fi ilẹ rere yi fun ọ lati ní i nitori ododo rẹ; nitoripe enia ọlọrùn lile ni iwọ. 7 Ranti, máṣe gbagbé, bi iwọ ti mu OLUWA Ọlọrun rẹ binu li aginjù: lati ọjọ́ na ti iwọ ti jade kuro ni ilẹ Egipti, titi ẹnyin fi dé ihin yi, ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA. 8 Ati ni Horebu ẹnyin mu OLUWA binu, OLUWA si binu si nyin tobẹ̃ ti o fẹ́ pa nyin run. 9 Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi. 10 OLUWA si fi walã okuta meji fun mi, ti a fi ika Ọlọrun kọ; ati lara wọn li a kọ ọ gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ na, ti OLUWA bá nyin sọ li òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì. 11 O si ṣe li opin ogoji ọsán ati ogoji oru, ti OLUWA fi walã okuta meji nì fun mi, ani walã majẹmu nì. 12 OLUWA si wi fun mi pe, Dide, sọkalẹ kánkán lati ihin lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú lati ilẹ Egipti jade wá, ti bà ara wọn jẹ́; nwọn yipada kánkán kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun wọn; nwọn ti yá ere didà fun ara wọn. 13 OLUWA sọ fun mi pẹlu pe, Emi ti ri enia yi, si kiyesi i, enia ọlọrùn lile ni: 14 Yàgo fun mi, ki emi ki o pa wọn run, ki emi si pa orukọ wọn rẹ́ kuro labẹ ọrun: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède ti o lagbara ti o si pọ̀ jù wọn lọ. 15 Emi si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke nì wá, òke na si njóna: walã meji ti majẹmu nì si wà li ọwọ́ mi mejeji. 16 Mo si wò, si kiyesi i, ẹnyin ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin si ti yá ẹgbọrọ-malu didà fun ara nyin: ẹnyin ti yipada kánkán kuro li ọ̀na ti OLUWA ti palaṣẹ fun nyin. 17 Emi si mú walã meji nì, mo si sọ wọn silẹ kuro li ọwọ́ mi mejeji, mo si fọ́ wọn niwaju nyin. 18 Emi si wolẹ niwaju OLUWA bi ti iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru; emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kò mu omi; nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin ti ẹnyin ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju OLUWA, lati mu u binu. 19 Nitoriti emi bẹ̀ru ibinu ati irunu OLUWA si nyin lati pa nyin run. OLUWA si gbọ́ ti emi nigbana pẹlu. 20 OLUWA si binu si Aaroni gidigidi ti iba fi pa a run: emi si gbadura fun Aaroni nigbana pẹlu. 21 Emi si mú ẹ̀ṣẹ nyin, ẹgbọrọ-malu ti ẹnyin ṣe, mo si fi iná sun u, mo si gún u, mo si lọ̀ ọ kúnna, titi o fi dabi ekuru: mo si kó ekuru rẹ̀ lọ idà sinu odò ti o ti òke na ṣànwalẹ. 22 Ati ni Tabera, ati ni Massa, ati ni Kibrotu-hattaafa, ẹnyin mu OLUWA binu. 23 Nigbati OLUWA rán nyin lati Kadeṣi-barnea lọ, wipe, Gòke lọ ki o si gbà ilẹ na ti mo fi fun nyin; nigbana li ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin kò si gbà a gbọ́, bẹ̃li ẹnyin kò si fetisi ohùn rẹ̀. 24 Ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA lati ọjọ́ ti mo ti mọ̀ nyin. 25 Mo si wolẹ niwaju OLUWA li ogoji ọsán ati li ogoji oru, bi mo ti wolẹ niṣaju; nitoriti OLUWA wipe, on o run nyin. 26 Mo si gbadura sọdọ OLUWA wipe, Oluwa ỌLỌRUN, máṣe run awọn enia rẹ ati iní rẹ, ti iwọ ti fi titobi rẹ̀ ràsilẹ, ti iwọ mú lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara. 27 Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu awọn iranṣẹ rẹ; máṣe wò agídi awọn enia yi, tabi ìwabuburu wọn, tabi ẹ̀ṣẹ wọn: 28 Ki awọn enia ilẹ na ninu eyiti iwọ ti mú wa jade wá ki o má ba wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú wọn dé ilẹ na ti o ti ṣe ileri fun wọn, ati nitoriti o korira wọn, li o ṣe mú wọn jade wá lati pa wọn li aginjù. 29 Ṣugbọn sibẹ̀ enia rẹ ni nwọn iṣe, ati iní rẹ, ti iwọ mú jade nipa agbara nla rẹ, ati nipa ninà apa rẹ.

Deuteronomi 10

Mose Tún Gba Òfin

1 NIGBANA li OLUWA wi fun mi pe, Gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju, ki o si tọ̀ mi wá lori òke na, ki o si ṣe apoti igi kan. 2 Emi o si kọ ọ̀rọ ti o ti wà lara walã iṣaju ti iwọ fọ́, sara walã wọnyi, iwọ o si fi wọn sinu apoti na. 3 Emi si ṣe apoti igi ṣittimu kan, mo si gbẹ́ walã okuta meji bi ti isaju, mo si lọ sori òke na, walã mejeji si wà li ọwọ́ mi. 4 On si kọ ofin mẹwẹwa sara walã wọnni, gẹgẹ bi o ti kọ ti iṣaju, ti OLUWA sọ fun nyin lori òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì; OLUWA si fi wọn fun mi. 5 Mo si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke na wá, mo si fi walã wọnni sinu apoti ti mo ti ṣe; nwọn si wà nibẹ̀, bi OLUWA ti paṣẹ fun mi. 6 (Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati Beerotu ti iṣe ti awọn ọmọ Jaakani lọ si Mosera: nibẹ̀ li Aaroni gbé kú, nibẹ̀ li a si sin i; Eleasari ọmọ rẹ̀ si nṣe iṣẹ alufa ni ipò rẹ̀. 7 Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Gudgoda; ati lati Gudgoda lọ si Jotbati, ilẹ olodò omi. 8 Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi. 9 Nitorina ni Lefi kò ṣe ní ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; OLUWA ni iní rẹ̀, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun ti ṣe ileri fun u.) 10 Emi si duro lori òke na, gẹgẹ bi ìgba iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru: OLUWA si gbọ́ ti emi ni igbana pẹlu, OLUWA kò si fẹ́ run ọ. 11 OLUWA si wi fun mi pe, Dide, mú ọ̀na ìrin rẹ niwaju awọn enia, ki nwọn ki o le wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki nwọn ki o le gbà ilẹ na, ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.

Ohun Tí Ọlọrun Ń Bèèrè

12 Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, 13 Lati ma pa ofin OLUWA mọ́, ati ìlana rẹ̀, ti mo filelẹ fun ọ li aṣẹ li oni, fun ire rẹ? 14 Kiyesi i, ti OLUWA Ọlọrun rẹ li ọrun, ati ọrun dé ọrun, aiye pẹlu, ti on ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀. 15 Kìki OLUWA ni inudidùn si awọn baba rẹ lati fẹ́ wọn, on si yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, ani ẹnyin jù gbogbo enia lọ, bi o ti ri li oni yi. 16 Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́. 17 Nitori OLUWA Ọlọrun nyin, Ọlọrun awọn ọlọrun ni ati OLUWA awọn oluwa, Ọlọrun titobi, alagbara, ati ẹ̀lẹru, ti ki iṣe ojuṣaju, bẹ̃ni ki igba abẹtẹlẹ. 18 On ni ima ṣe idajọ alainibaba ati opó, o si fẹ́ alejò, lati fun u li onjẹ ati aṣọ. 19 Nitorina ki ẹnyin ki o ma fẹ́ alejò: nitoripe ẹnyin ṣe alejò ni ilẹ Egipti. 20 Ki iwọ ki o ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ; on ni ki iwọ ki o ma sìn, on ni ki iwọ ki o si faramọ́, orukọ rẹ̀ ni ki o si ma fi bura. 21 On ni iyìn rẹ, on si li Ọlọrun rẹ, ti o ṣe ohun nla ati ohun ẹ̀lẹru wọnni fun ọ, ti oju rẹ ri. 22 Awọn baba rẹ sọkalẹ lọ si Egipti ti awọn ti ãdọrin enia; ṣugbọn nisisiyi OLUWA Ọlọrun rẹ sọ ọ dabi irawọ ọrun li ọ̀pọlọpọ.

Deuteronomi 11

Títóbi OLUWA

1 NITORINA ki iwọ ki o fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma pa ikilọ̀ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ofin rẹ̀ mọ́, nigbagbogbo. 2 Ki ẹnyin ki o si mọ̀ li oni: nitoripe awọn ọmọ nyin ti emi nsọ fun ti kò mọ̀, ti kò si ri ibawi OLUWA Ọlọrun nyin, titobi rẹ̀, ọwọ́ agbara rẹ̀, ati ninà apa rẹ̀, 3 Ati iṣẹ-àmi rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, ti o ṣe lãrin Egipti, si Farao ọba Egipti, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀; 4 Ati ohun ti o ṣe si ogun Egipti, si ẹṣin wọn, ati kẹkẹ́-ogun wọn; bi o ti mu ki omi Okun Pupa bò wọn mọlẹ bi nwọn ti nlepa nyin lọ, ati bi OLUWA ti run wọn titi di oni-oloni; 5 Ati bi o ti ṣe si nyin li aginjù, titi ẹnyin fi dé ihin yi; 6 Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli: 7 Ṣugbọn oju nyin ti ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA ti o ṣe.

Ibukun Ilẹ̀ Ìlérí náà

8 Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a; 9 Ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 10 Nitoripe ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, kò dabi ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin ti jade wá, nibiti iwọ gbìn irugbìn rẹ, ti iwọ si nfi ẹsẹ̀ rẹ bomirin i, bi ọgbà ewebẹ̀: 11 Ṣugbọn ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a, ilẹ òke ati afonifoji ni, ti o si nmu omi òjo ọrun: 12 Ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ nṣe itọju; oju OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lara rẹ̀ nigbagbogbo, lati ìbẹrẹ ọdún dé opin ọdún. 13 Yio si ṣe, bi ẹnyin ba fetisi ofin mi daradara, ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo, ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo, 14 Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile. 15 Emi o si fi koriko sinu pápa rẹ fun ohunọ̀sin rẹ, ki iwọ ki o le jẹun ki o si yó. 16 Ẹ ma ṣọ́ ara nyin, ki a má ba tàn àiya nyin jẹ, ki ẹ má si ṣe yapa, ki ẹ si sìn ọlọrun miran, ki ẹ si ma bọ wọn; 17 Ibinu OLUWA a si rú si nyin, on a si sé ọrun, ki òjo ki o má ba sí, ati ki ilẹ ki o má ba so eso rẹ̀; ẹnyin a si run kánkán kuro ni ilẹ rere na ti OLUWA fi fun nyin. 18 Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin. 19 Ki ẹnyin ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide. 20 Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun-ọ̀na-ode rẹ: 21 Ki ọjọ́ nyin ki o le ma pọ̀si i, ati ọjọ́ awọn ọmọ nyin, ni ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin lati fi fun wọn, bi ọjọ́ ọrun lori ilẹ aiye. 22 Nitoripe bi ẹnyin ba pa gbogbo ofin yi mọ́ gidigidi, ti mo palaṣẹ fun nyin, lati ma ṣe e; lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati faramọ́ ọ; 23 Nigbana ni OLUWA yio lé gbogbo awọn orilẹ-ède wọnyi jade kuro niwaju nyin, ẹnyin o si gbà orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù nyin lọ. 24 Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀ yio jẹ́ ti nyin: lati aginjù nì, ati Lebanoni, lati odò nla nì, odò Euferate, ani dé ikẹhin okun ni yio jẹ́ opinlẹ nyin. 25 Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin. 26 Wò o, emi fi ibukún ati egún siwaju nyin li oni; 27 Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni: 28 Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí. 29 Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, ki iwọ ki o ma sure lori òke Gerisimu, ki iwọ ki o si ma gegun lori òke Ebali. 30 Awọn kọ ha wà ni ìha keji Jordani, li ọ̀na ìwọ-õrùn, ni ilẹ awọn ara Kenaani, ti ngbé Araba ti o kọjusi Gilgali, lẹba igbó More? 31 Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀. 32 Ki ẹnyin ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gbogbo ìlana ati idajọ wọnni, ti mo fi siwaju nyin li oni.

Deuteronomi 12

Ibi Ìjọ́sìn Kanṣoṣo Náà

1 WỌNYI ni ìlana ati idajọ, ti ẹnyin o ma kiyesi lati ma ṣe ni ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ fi fun ọ lati ní, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà lori ilẹ-aiye. 2 Ki ẹnyin ki o run ibi gbogbo wọnni patapata, nibiti awọn orilẹ-ède nì, ti ẹnyin o gbà, nsìn oriṣa wọn, lori òke giga, ati lori òke kekeké, ati labẹ igi tutù gbogbo: 3 Ki ẹnyin ki o si wó pẹpẹ wọn, ki ẹ si bì ọwọ̀n wọn ṣubu, ki ẹ si fi iná kun igbo oriṣa wọn; ki ẹnyin ki o si ke ere fifin wọn lulẹ, ki ẹ si run orukọ wọn kuro ni ibẹ na. 4 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin. 5 Ṣugbọn ibi ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn ninu gbogbo ẹ̀ya nyin lati fi orukọ rẹ̀ si, ani ibujoko rẹ̀ li ẹnyin o ma wálọ, ati nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma wá: 6 Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o ma mú ẹbọ sisun nyin wá, ati ẹbọ nyin, ati idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ifẹ́-atinuwa nyin, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran nyin ati ti agbo-ẹran nyin: 7 Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ma jẹ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ ninu ohun gbogbo ti ẹnyin fi ọwọ́ nyin lé, ẹnyin ati awọn ara ile nyin, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún u fun ọ. 8 Ki ẹnyin ki o máṣe ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awa nṣe nihin li oni, olukuluku enia ohun ti o tọ́ li oju ara rẹ̀: 9 Nitoripe ẹnyin kò sá ti idé ibi-isimi, ati ilẹ iní, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin. 10 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gòke Jordani, ti ẹnyin si joko ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin ni iní, ti o ba si fun nyin ni isimi kuro lọwọ awọn ọtá nyin gbogbo yiká, ti ẹnyin si joko li alafia: 11 Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA. 12 Ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin, ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode nyin, nitori on kò ní ipín tabi iní pẹlu nyin. 13 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe ru ẹbọ sisun rẹ ni ibi gbogbo ti iwọ ba ri: 14 Bikoṣe ni ibi ti OLUWA yio yàn ninu ọkan ninu awọn ẹ̀ya rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ. 15 Ṣugbọn ki iwọ ki o ma pa, ki o si ma jẹ ẹran ninu ibode rẹ gbogbo, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ ni ki o ma jẹ ninu rẹ̀, bi esuro, ati bi agbọnrin. 16 Kìki ẹ̀jẹ li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; lori ilẹ ni ki ẹ dà a si bi omi. 17 Ki iwọ ki o máṣe jẹ idamẹwa ọkà rẹ ninu ibode rẹ, tabi ti ọti-waini rẹ, tabi ti oróro rẹ, tabi ti akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, tabi ti agbo-ẹran rẹ, tabi ti ẹjẹ́ rẹ ti iwọ jẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwa rẹ, tabi ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ rẹ: 18 Bikoṣe ki iwọ ki o jẹ wọn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ: ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ninu ohun gbogbo ti iwọ fi ọwọ́ rẹ le. 19 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe kọ̀ ọmọ Lefi silẹ ni gbogbo ọjọ́ rẹ lori ilẹ. 20 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ti iwọ ba si wipe, Emi o jẹ ẹran, nitoriti ọkàn rẹ nfẹ́ ẹran ijẹ; ki iwọ ki o ma jẹ ẹran, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ́. 21 Bi o ba ṣepe, ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ ba yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si, ba jìna jù fun ọ, njẹ ki iwọ ki o pa ninu ọwọ́-ẹran rẹ ati ninu agbo-ẹran rẹ, ti OLUWA fi fun ọ, bi emi ti fi aṣẹ fun o, ki iwọ ki o si ma jẹ ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́ ninu ibode rẹ. 22 Ani bi ã ti ijẹ esuro, ati agbọnrin, bẹ̃ni ki iwọ ki o ma jẹ wọn: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ yio jẹ ninu wọn bakanna. 23 Kìki ki o ṣọ́ ara rẹ gidigidi ki iwọ ki o máṣe jẹ ẹ̀jẹ: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi; iwọ kò si gbọdọ jẹ ẹmi pẹlu ẹran. 24 Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; iwọ o dà a silẹ bi omi. 25 Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; ki o le ma dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA. 26 Kìki ohun mimọ́ rẹ ti iwọ ní, ati ẹjẹ́ rẹ ni ki iwọ ki o mú, ki o si lọ si ibi ti OLUWA yio yàn: 27 Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun rẹ, ẹran ati ẹ̀jẹ na, lori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ati ẹ̀jẹ ẹbọ rẹ ni ki a dà sori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma jẹ ẹran na. 28 Kiyesara ki o si ma gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti mo palaṣẹ fun ọ, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ lailai, nigbati iwọ ba ṣe eyiti o dara ti o si tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ. 29 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro niwaju rẹ, nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà wọn, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilẹ wọn; 30 Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ má ba bọ́ si idẹkùn ati tẹle wọn lẹhin, lẹhin igbati a ti run wọn kuro niwaju rẹ; ki iwọ ki o má si bère oriṣa wọn, wipe, Bawo li awọn orilẹ-ède wọnyi ti nsìn oriṣa wọn? emi o si ṣe bẹ̃ pẹlu. 31 Iwọ kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe gbogbo ohun irira si OLUWA, ti on korira ni nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; nitoripe awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin wọn pẹlu ni nwọn nsun ninu iná fun oriṣa wọn. 32 Ohunkohun ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin, ẹ ma kiyesi lati ṣe e: iwọ kò gbọdọ fikún u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀.

Deuteronomi 13

1 BI wolĩ kan ba hù lãrin rẹ, tabi alalá kan, ti o si fi àmi tabi iṣẹ́-iyanu kan hàn ọ, 2 Ti àmi na tabi iṣẹ-iyanu na ti o sọ fun ọ ba ṣẹ, wipe, Ẹ jẹ ki a tẹlé ọlọrun miran lẹhin, ti iwọ kò ti mọ̀ rí, ki a si ma sìn wọn; 3 Iwọ kò gbọdọ fetisi ọ̀rọ wolĩ na, tabi alalá na: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ndan nyin wò ni, lati mọ̀ bi ẹnyin ba fi gbogbo àiya nyin, ati gbogbo ọkàn nyin fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin. 4 Lẹhin OLUWA Ọlọrun nyin ni ki ẹnyin ki o ma rìn, on ni ki ẹ si ma bẹ̀ru, ki ẹ si ma pa ofin rẹ̀ mọ́, ki ẹ si ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ki ẹ si ma sìn i, ki ẹ si ma faramọ́ ọ. 5 Ati wolĩ na, tabi alalá na, ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sẹ ọtẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ti o ti rà nyin kuro li oko-ẹrú, lati tì ọ kuro li oju ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rìn ninu rẹ̀. Bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ibi kuro lãrin rẹ. 6 Bi arakunrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ́ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti iwọ kò mọ̀ rí, iwọ, tabi awọn baba rẹ; 7 Ninu awọn oriṣa awọn enia ti o yi nyin kakiri, ti o sunmọ ọ, tabi ti o jìna si ọ, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; 8 Iwọ kò gbọdọ jẹ fun u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fetisi tirẹ̀; bẹ̃ni ki oju ki o máṣe ro ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe da a si, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe bò o: 9 Ṣugbọn pipa ni ki o pa a; ọwọ́ rẹ ni yio kọ́ wà lara rẹ̀ lati pa a, ati lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. 10 Ki iwọ ki o si sọ ọ li okuta, ki o kú; nitoriti o nwá ọ̀na lati tì ọ kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú. 11 Gbogbo Israeli yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù ìwabuburu bi irú eyi mọ́ lãrin nyin. 12 Bi iwọ ba gbọ́ ninu ọkan ninu awọn ilu rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ma gbé inu rẹ̀ pe, 13 Awọn ọkunrin kan, awọn ọmọ Beliali, nwọn jade lọ kuro ninu nyin, nwọn si kó awọn ara ilu wọn sẹhin, wipe, Ẹ jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti ẹnyin kò mọ̀ rí. 14 Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ; si kiyesi i, bi o ba ṣe otitọ, ti ohun na ba si da nyin loju, pe a ṣe irú nkan irira bẹ̃ ninu nyin; 15 Ki iwọ ki o fi oju idà kọlù awọn ara ilu na nitõtọ, lati run u patapata, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ohunọ̀sin inu rẹ̀, ni ki iwọ ki o fi oju idà pa. 16 Ki iwọ ki o si kó gbogbo ikogun rẹ̀ si ãrin igboro rẹ̀, ki iwọ ki o si fi iná kun ilu na, ati gbogbo ikogun rẹ̀ patapata fun OLUWA Ọlọrun rẹ: ki o si ma jasi òkiti lailai; a ki yio si tun tẹ̀ ẹ dó mọ́. 17 Ki ọkan ninu ohun ìyasọtọ na má si ṣe mọ́ ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ; 18 Nigbati iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ofin rẹ̀ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.

Deuteronomi 14

Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀

1 ỌMỌ OLUWA Ọlọrun nyin li ẹnyin iṣe: ẹnyin kò gbọdọ̀ bù ara nyin li abẹ, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fá iwaju nyin nitori okú. 2 Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, OLUWA si ti yàn ọ lati ma ṣe enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo orilẹ-ède lọ ti mbẹ lori ilẹ.

Ẹran Tí Ó Mọ́ ati Èyí Tí Kò Mọ́

3 Iwọ kò gbọdọ jẹ ohun irira kan. 4 Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ: akọmalu, agutan, ati ewurẹ, 5 Agbọnrin, ati esuwo, ati gala, ati ewurẹ igbẹ́, ati pigargi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu. 6 Ati gbogbo ẹranko ti o là bàta-ẹsẹ̀, ti o si pinyà bàta-ẹsẹ̀ si meji, ti o si njẹ apọjẹ ninu ẹranko, eyinì ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 7 Ṣugbọn wọnyi ni ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi ninu awọn ti o là bàta-ẹsẹ̀; bi ibakasiẹ, ati ehoro, ati garà, nitoriti nwọn njẹ apọjẹ ṣugbọn nwọn kò là bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin: 8 Ati ẹlẹdẹ̀, nitoriti o là bàta-ẹsẹ̀ ṣugbọn kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ ni fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn okú wọn. 9 Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo eyiti mbẹ ninu omi: gbogbo eyiti o ní lẹbẹ ti o si ní ipẹ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 10 Ati ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ti kò si ní ipẹ́, ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ẹ; alaimọ́ ni fun nyin. 11 Gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 12 Ṣugbọn wọnyi li awọn ti ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu wọn: idì, ati aṣa-idì, ati idì-ẹja. 13 Ati glede, ati aṣá, ati gunugun li onirũru rẹ̀; 14 Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀; 15 Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀; 16 Owiwi kekere, ati owiwi nla, ati ogbugbu; 17 Ati pelikan, ati àkala, ati ìgo; 18 Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán. 19 Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn. 20 Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ. 21 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.

Òfin nípa Ìdámẹ́wàá

22 Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún. 23 Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo. 24 Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ: 25 Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn. 26 Ki iwọ ki o si ná owo na si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, si akọmalu, tabi agutan, tabi ọti-waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́: ki iwọ ki o si ma jẹ nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma yọ̀, iwọ, ati awọn ara ile rẹ: 27 Ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ; iwọ kò gbọdọ kọ̀ ọ silẹ; nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ. 28 Li opin ọdún mẹta ni ki iwọ ki o mú gbogbo idamẹwa ibisi rẹ wa li ọdún na, ki iwọ ki o si gbé e kalẹ ninu ibode rẹ: 29 Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.

Deuteronomi 15

Ọdún Keje

1 LẸHIN ọdún mejemeje ni ki iwọ ki o ma ṣe ijọwọlọwọ. 2 Ọ̀na ijọwọlọwọ na si li eyi: gbogbo onigbese ti o wín ẹnikeji rẹ̀ ni nkan ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ; ki o ma ṣe fi agbara bère rẹ̀ lọwọ ẹnikeji rẹ̀, tabi lọwọ arakunrin rẹ̀; nitoriti a pè e ni ijọwọlọwọ OLUWA. 3 Iwọ le fi agbara bère lọwọ alejò: ṣugbọn eyiti ṣe tirẹ ti mbẹ li ọwọ́ arakunrin rẹ, ni ki iwọ ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ. 4 Ṣugbọn ki yio sí talaka ninu nyin; (nitoripe OLUWA yio busi i fun ọ pupọ̀ ni ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati gbà a;) 5 Kìki bi iwọ ba fi ifarabalẹ fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi gbogbo ofin yi, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni lati ṣe. 6 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ, bi o ti ṣe ileri fun ọ: iwọ o si ma wín ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn iwọ ki yio tọrọ; iwọ o si ma ṣe olori ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn nwọn ki yio ṣe olori rẹ. 7 Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ: 8 Sugbọn lilà ni ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun u, ki iwọ ki o si wín i li ọ̀pọlọpọ tó fun ainí rẹ̀, li ohun ti nfẹ́. 9 Ma kiyesara ki ìro buburu kan ki o máṣe sí ninu àiya rẹ, wipe, Ọdún keje, ọdún ijọwọlọwọ sunmọtosi; oju rẹ a si buru si arakunrin rẹ talakà, ti iwọ kò si fun u ni nkan; on a si kigbe pè OLUWA nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ fun ọ. 10 Ki iwọ ki o fi fun u nitõtọ, ki inu rẹ ki o máṣe bàjẹ́ nigbati iwọ ba fi fun u: nitoripe nitori nkan yi ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo iṣẹ rẹ, ati ni gbogbo ohun ti iwọ ba dá ọwọ́ rẹ lé. 11 Nitoripe talakà kò le tán ni ilẹ na: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun arakunrin rẹ, fun talakà rẹ, ati fun alainí rẹ, ninu ilẹ rẹ.

Ìlò Ẹrú

12 Ati bi a ba tà arakunrin rẹ kan fun ọ, ọkunrin Heberu, tabi obinrin Heberu, ti o si sìn ọ li ọdún mẹfa; njẹ li ọdún keje ki iwọ ki o rán a lọ kuro lọdọ rẹ li ominira. 13 Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo: 14 Ki iwọ ki o pèse fun u li ọ̀pọlọpọ lati inu agbo-ẹran rẹ wá, ati lati ilẹ-ipakà rẹ, ati lati ibi ifunti rẹ, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún ọ ni ki iwọ ki o fi fun u. 15 Ki iwọ ki o si ranti pe, iwọ a ti ma ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ: nitorina ni mo ṣe fi aṣẹ nkan yi lelẹ fun ọ li oni. 16 Yio si ṣe, bi o ba wi fun ọ pe, Emi ki yio jade lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o fẹ́ ọ ati ile rẹ, nitoriti o dara fun u lọdọ rẹ; 17 Nigbana ni ki iwọ ki o mú olu kan, ki iwọ ki o si fi lu u li etí mọ́ ara ilẹkun, ki on ki o si ma ṣe ọmọ-ọdọ rẹ lailai. Ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ni ki iwọ ki o ṣe bẹ̃ si gẹgẹ. 18 Ki o máṣe ro ọ loju, nigbati iwọ ba rán a li ominira lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o ní iye lori to alagbaṣe meji ni sísìn ti o sìn ọ li ọdún mẹfa: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si busi i fun ọ ninu gbogbo ohun ti iwọ nṣe.

Àkọ́bí Mààlúù ati ti Aguntan

19 Gbogbo akọ́bi akọ ti o ti inu ọwọ-ẹran rẹ ati inu agbo-eran rẹ wá, ni ki iwọ ki o yàsi-mimọ́, fun OLUWA Ọlọrun rẹ: iwọ kò gbọdọ fi akọ́bi ninu akọmalu rẹ ṣe iṣẹ kan, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹrun akọ́bi agutan rẹ, 20 Ki iwọ ki o ma jẹ ẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ọdọdún, ni ibi ti OLUWA yio yàn, iwọ, ati awọn ara ile rẹ. 21 Bi abùku kan ba si wà lara rẹ̀, bi o mukun ni, bi o fọju ni, tabi bi o ni abùku buburu kan, ki iwọ ki o máṣe fi rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ. 22 Ki iwọ ki o jẹ ẹ ninu ibode rẹ: alaimọ́ ati ẹni ti o mọ́ ni ki o jẹ ẹ bakanna, bi esuwo, ati bi agbọnrin. 23 Kìki iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ rẹ̀; ki iwọ ki o dà a silẹ bi omi.

Deuteronomi 16

Àjọ Ìrékọjá

1 IWỌ ma kiyesi oṣù Abibu, ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe li oṣù Abibu ni OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ilẹ Egipti jade wa li oru. 2 Nitorina ki iwọ ki o ma pa ẹran irekọja si OLUWA Ọlọrun rẹ, ninu agbo-ẹran ati ninu ọwọ́-ẹran, ni ibi ti OLUWA yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si. 3 Iwọ kò gbọdọ jẹ àkara wiwu pẹlu rẹ̀; ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu pẹlu rẹ̀, ani onjẹ ipọnju; nitoripe iwọ ti ilẹ Egipti jade wá ni kanjukanju: ki iwọ ki o le ma ranti ọjọ́ ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wa, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo. 4 Ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ li àgbegbe rẹ gbogbo ni ijọ́ meje; bẹ̃ni ki ohun kan ninu ẹran ti iwọ o fi rubọ li ọjọ́ kini li aṣalẹ, ki o máṣe kù di owurọ̀. 5 Ki iwọ ki o máṣe pa ẹran irekọja na ninu ibode rẹ kan, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ: 6 Ṣugbọn bikoṣe ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o pa ẹran irekọja na li aṣalẹ, nigba ìwọ-õrùn, li akokò ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wá. 7 Ki iwọ ki o si sun u, ki iwọ ki o si jẹ ẹ ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn: ki iwọ ki o si pada li owurọ̀, ki o si lọ sinu agọ́ rẹ. 8 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu: ati ni ijọ́ keje ki ajọ kan ki o wà fun OLUWA Ọlọrun rẹ; ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹ́ kan.

Àjọ̀dún Ìkórè

9 Ọsẹ meje ni ki iwọ ki o kà fun ara rẹ: bẹ̀rẹsi ati kà ọ̀sẹ meje na lati ìgba ti iwọ ba tẹ̀ doje bọ̀ ọkà. 10 Ki iwọ ki o si pa ajọ ọ̀sẹ mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu ọrẹ ifẹ́-atinuwa ọwọ́ rẹ, ti iwọ o fi fun u, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti busi i fun ọ: 11 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ lãrin rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si. 12 Ki iwọ ki o si ma ranti pe, ẹrú ni iwọ ti jẹ́ ni Egipti: ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ṣe ìlana wọnyi.

Àjọ̀dún Àgọ́

13 Ki iwọ ki o si ma pa ajọ agọ́ mọ́ li ọjọ́ meje, lẹhin ìgba ti iwọ ba ṣe ipalẹmọ ilẹ-ipakà rẹ ati ibi-ifunti rẹ. 14 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ. 15 Ijọ́ meje ni ki iwọ ki o fi ṣe ajọ si OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti OLUWA yio yàn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo asunkún rẹ, ati ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, nitorina ki iwọ ki o ma yọ̀ nitõtọ. 16 Lẹ̃mẹta li ọdún ni ki gbogbo awọn ọkunrin rẹ ki o farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn; ni ajọ àkara alaiwu, ati ni ajọ ọ̀sẹ, ati ni ajọ agọ́: ki nwọn ki o má si ṣe ṣánwọ wá iwaju OLUWA: 17 Ki olukuluku ki o mú ọrẹ wá bi agbara rẹ̀ ti to, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ.

Ìlànà nípa Ẹjọ́ Dídá

18 Awọn onidajọ ati awọn ijoye ni ki iwọ ki o fi jẹ ninu ibode rẹ gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, gẹgẹ bi ẹ̀ya rẹ: ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia na li ododo. 19 Iwọ kò gbọdọ lọ́ idajọ; iwọ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju enia: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbà ẹ̀bun; nitoripe ẹ̀bun ni ifọ́ ọlọgbọ́n li oju, on a si yi ọ̀rọ olododo po. 20 Eyiti iṣe ododo patapata ni ki iwọ ki o ma tọ̀ lẹhin, ki iwọ ki o le yè, ki iwọ ki o si ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 21 Iwọ kò gbọdọ rì igi oriṣa kan sunmọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ o mọ fun ara rẹ. 22 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbé ọwọ̀n kan kalẹ fun ara rẹ: ti OLUWA Ọlọrun rẹ korira.

Deuteronomi 17

1 IWỌ kò gbọdọ fi akọmalu, tabi agutan, ti o lí àbuku, tabi ohun buburu kan rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ. 2 Bi a ba ri lãrin nyin, ninu ibode rẹ kan ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ọkunrin tabi obinrin ti nṣe nkan buburu li oju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni rire majẹmu rẹ̀ kọja, 3 Ti o si lọ ti o nsìn ọlọrun miran, ti o si mbọ wọn, iba ṣe õrùn, tabi oṣupa, tabi ọkan ninu ogun ọrun, ti emi kò palaṣẹ; 4 Ti a ba si wi fun ọ, ti iwọ si ti gbọ́, ti iwọ si wádi rẹ̀ rere, si kiyesi i, ti o jasi otitọ, ti ohun na si daniloju pe, a ṣe irú irira yi ni Israeli; 5 Nigbana ni ki iwọ ki o mú ọkunrin tabi obinrin na, ti o ṣe ohun buburu yi jade wá, si ibode rẹ, ani ọkunrin tabi obinrin na, ki iwọ ki o si sọ wọn li okuta pa. 6 Li ẹnu ẹlẹri meji, tabi ẹlẹri mẹta, li a o pa ẹniti o yẹ si ikú; ṣugbọn li ẹnu ẹlẹri kan, a ki yio pa a. 7 Ọwọ́ awọn ẹlẹri ni yio tète wà lara rẹ̀ lati pa a, lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. Bẹ̃ni iwọ o si mú ìwabuburu kuro lãrin nyin. 8 Bi ẹjọ́ kan ba ṣoro jù fun ọ lati dá, lãrin èjẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ọ̀ran on ọ̀ran, ati lãrin ìluni ati ìluni, ti iṣe ọ̀ran iyàn ninu ibode rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o dide, ki o si gòke lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn; 9 Ki iwọ ki o si tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi lọ, ati onidajọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni: ki o si bère; nwọn o si fi ọ̀rọ idajọ hàn ọ: 10 Ki iwọ ki o si ṣe bi ọ̀rọ idajọ, ti awọn ará ibi ti OLUWA yio yàn na yio fi hàn ọ; ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti nwọn kọ́ ọ: 11 Gẹgẹ bi ọ̀rọ ofin ti nwọn o kọ́ ọ, ati gẹgẹ bi idajọ ti nwọn o wi fun ọ, ni ki iwọ ki o ṣe: ki iwọ ki o máṣe yà si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi, kuro li ọ̀rọ ti nwọn o fi hàn ọ. 12 Ọkunrin na ti o ba si fi igberaga ṣe e, ti kò fẹ́ gbọ́ ti alufa na, ti o duro lati ma ṣe iṣẹ alufa nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, tabi lati gbọ́ ti onidajọ na, ani ọkunrin na yio kú: iwọ o si mú ìwabuburu kuro ni Israeli. 13 Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.

Ìkìlọ̀ nípa Yíyan Ọba

14 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká; 15 Kìki ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn, ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ọkan ninu awọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ki iwọ ki o máṣe fi alejò ṣe olori rẹ, ti ki iṣe arakunrin rẹ. 16 Ṣugbọn on kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe mu awọn enia pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹṣin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, Ẹnyin kò gbọdọ tun pada lọ li ọ̀na na mọ́. 17 Bẹ̃ni ki o máṣe kó obinrin jọ fun ara rẹ̀, ki àiya rẹ̀ ki o má ba yipada: bẹ̃ni ki o máṣe kó fadakà tabi wurá jọ fun ara rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ. 18 Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi: 19 Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn: 20 Ki àiya rẹ̀ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ́ rẹ̀ pẹ ni ijọba rẹ̀, on, ati awọn ọmọ rẹ̀, lãrin Israeli.

Deuteronomi 18

Ìpín Àwọn Àlùfáàa

1 AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ. 2 Nitorina ni nwọn ki yio ṣe ni iní lãrin awọn arakunrin wọn: OLUWA ni iní wọn, bi o ti wi fun wọn. 3 Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo. 4 Akọ́so ọkà rẹ pẹlu, ati ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́rẹ irun agutan rẹ, ni ki iwọ ki o fi fun u. 5 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ li o yàn a ninu gbogbo awọn ẹ̀ya rẹ, lati ma duro ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai. 6 Ati bi ọmọ Lefi kan ba ti inu ibode rẹ kan wá, ni gbogbo Israeli, nibiti o gbé nṣe atipo, ti o si fi gbogbo ifẹ́ inu rẹ̀ wá si ibi ti OLUWA yio yàn; 7 Njẹ ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, bi gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Lefi, ti nduro nibẹ̀ niwaju OLUWA. 8 Ipín kanna ni ki nwọn ki o ma jẹ, làika eyiti o ní nipa tità ogún baba rẹ̀.

Ìkìlọ̀ nípa Àwọn Àṣà Ìbọ̀rìṣà

9 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe kọ́ ati ṣe gẹgẹ bi ìwa-irira awọn orilẹ-ède wọnni. 10 Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́, 11 Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò. 12 Nitoripe gbogbo awọn ti nṣe nkan wọnyi irira ni si OLUWA: ati nitori irira wọnyi ni OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ. 13 Ki iwọ ki o pé lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ.

Ìlérí láti Rán Wolii Kan sí Israẹli

14 Nitori orilẹ-ède wọnyi ti iwọ o gbà, nwọn fetisi awọn alakiyesi-ìgba, ati si awọn alafọ̀ṣẹ: ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni, OLUWA Ọlọrun rẹ kò gbà fun ọ bẹ̃. 15 OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi; 16 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú. 17 OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ. 18 Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ. 19 Yio si ṣe, ẹniti kò ba fetisi ọ̀rọ mi ti on o ma sọ li orukọ mi, emi o bère lọwọ rẹ̀. 20 Ṣugbọn wolĩ na, ti o kùgbu sọ ọ̀rọ kan li orukọ mi, ti emi kò fi fun u li aṣẹ lati sọ, tabi ti o sọ̀rọ li orukọ ọlọrun miran, ani wolĩ na yio kú. 21 Bi iwọ ba si wi li ọkàn rẹ pe, Bawo li awa o ṣe mọ̀ ọ̀rọ ti OLUWA kò sọ? 22 Nigbati wolĩ kan ba sọ̀rọ li orukọ OLUWA, bi ohun na kò ba ri bẹ̃, ti kò ba si ṣẹ, eyinì li ohun ti OLUWA kò sọ: wolĩ na li o fi ikùgbu sọ̀rọ: ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru rẹ̀.

Deuteronomi 19

Àwọn ìlú Ààbò

1 NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro, ilẹ ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilu wọn, ati ni ile wọn; 2 Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ lãrin ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní. 3 Ki iwọ ki o là ọ̀na kan fun ara rẹ, ki iwọ ki o si pín àgbegbe ilẹ rẹ si ipa mẹta, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní, ki gbogbo apania ki o ma sá sibẹ̀. 4 Eyi si ni ọ̀ran apania, ti yio ma sá sibẹ̀, ki o le yè: ẹnikẹni ti o ba ṣeṣi pa ẹnikeji rẹ̀, ti on kò korira rẹ̀ tẹlẹrí; 5 Bi nigbati enia ba wọ̀ inu igbó lọ pélu ẹnikeji rẹ̀ lati ke igi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ gbé ãke lati fi ke igi na lulẹ, ti ãke si yọ kuro ninu erú, ti o si bà ẹnikeji rẹ̀, ti on kú; ki o salọ si ọkan ninu ilu wọnni, ki o si yè: 6 Ki agbẹsan ẹ̀jẹ ki o má ba lepa apania na, nigbati ọkàn rẹ̀ gboná, ki o si lé e bá, nitoriti ọ̀na na jìn, a si pa a; nigbati o jẹ pe kò yẹ lati kú, niwọnbi on kò ti korira rẹ̀ tẹlẹrí. 7 Nitorina emi fi aṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ. 8 Ati bi OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, ti on ti bura fun awọn baba rẹ, ti o sì fun ọ ni gbogbo ilẹ na, ti o si ṣe ileri fun awọn baba rẹ; 9 Bi iwọ ba pa gbogbo ofin yi mọ́ lati ma ṣe e, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati lati ma rìn titi li ọ̀na rẹ̀; nigbana ni ki iwọ ki o fi ilu mẹta kún u si i fun ara rẹ, pẹlu mẹta wọnyi; 10 Ki a má ba tà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ninu ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki ẹ̀jẹ ki o má ba wà li ọrùn rẹ. 11 Ṣugbọn bi ọkunrin kan ba korira ẹnikeji rẹ̀, ti o si ba dè e, ti o si dide si i, ti o si lù u li alupa, ti o si kú, ti on si salọ sinu ọkan ninu ilu wọnyi: 12 Njẹ ki awọn àgba ilu rẹ̀ ki o ránni ki nwọn ki o si mú u ti ibẹ̀ wá, ki nwọn ki o si fà a lé agbẹsan ẹ̀jẹ lọwọ ki o ba le kú. 13 Ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u, ṣugbọn ki iwọ ki o mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lori Israeli, ki o si le dara fun ọ.

Àwọn Ààlà Àtayébáyé

14 Iwọ kò gbọdọ yẹ̀ àla ẹnikeji rẹ, ti awọn ara iṣaju ti pa ni ilẹ iní rẹ ti iwọ o ní, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.

Àlàyé nípa Ẹlẹ́rìí

15 Ki ẹlẹri kanṣoṣo ki o máṣe dide jẹri tì enia nitori aiṣedede kan, tabi nitori ẹ̀ṣẹ kan ninu ẹ̀ṣẹ ti o ba ṣẹ̀: li ẹnu ẹlẹri meji, tabi li ẹnu ẹlẹri mẹta, li ọ̀ran yio fẹsẹmulẹ. 16 Bi ẹlẹri eké ba dide si ọkunrin lati jẹri tì i li ohun ti kò tọ́: 17 Njẹ ki awọn ọkunrin mejeji na lãrin ẹniti ọ̀rọ iyàn na gbé wà, ki o duro niwaju OLUWA, niwaju awọn alufa ati awọn onidajọ, ti yio wà li ọjọ wọnni, 18 Ki awọn onidajọ na ki o si tọ̀sẹ rẹ̀ pẹlẹpẹlẹ: si kiyesi i bi ẹlẹri na ba ṣe ẹlẹri eké, ti o si jẹri-eké si arakunrin rẹ̀; 19 Njẹ ki ẹnyin ki o ṣe si i, bi on ti rò lati ṣe si arakunrin rẹ̀: bẹ̃ni iwọ o si mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin. 20 Awọn ti o kù yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù irú ìwa-buburu bẹ̃ mọ́ lãrin nyin. 21 Ki oju rẹ ki o má si ṣe ṣãnu; ẹmi fun ẹmi, oju fun oju, ehín fun ehín, ọwọ́ fun ọwọ́, ẹsẹ̀ fun ẹsẹ̀.

Deuteronomi 20

Ọ̀rọ̀ nípa Ogun

1 NIGBATI iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti iwọ si ri ẹṣin, ati kẹkẹ́-ogun, ati awọn enia ti o pọ̀ jù ọ, máṣe bẹ̀ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá. 2 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba sunmọ ogun na, ki alufa ki o sunmọtosi, ki o si sọ̀rọ fun awọn enia. 3 Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn; 4 Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là. 5 Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i. 6 Ati ọkunrin wo li o gbìn ọgbà-àjara, ti kò si ti ijẹ ninu rẹ̀? jẹ ki on pẹlu ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba jẹ ẹ. 7 Ati ọkunrin wo li o fẹ́ iyawo, ti kò ti igbé e? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba gbé e. 8 Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkunrin wo li o wà ti o bẹ̀ru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki àiya awọn arakunrin rẹ̀ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ̀. 9 Yio si ṣe, nigbati awọn olori-ogun ba pari ọ̀rọ sisọ fun awọn enia tán, ki nwọn ki o si fi awọn balogun jẹ lori awọn enia na. 10 Nigbati iwọ ba sunmọ ilu kan lati bá a jà, nigbana ni ki iwọ ki o fi alafia lọ̀ ọ. 11 Yio si ṣe, bi o ba da ọ lohùn alafia, ti o si ṣilẹkun silẹ fun ọ, njẹ yio ṣe, gbogbo awọn enia ti a ba bá ninu rẹ̀, nwọn o si ma jẹ́ ọlọsin fun ọ, nwọn o si ma sìn ọ. 12 Bi kò ba si fẹ́ bá ọ ṣe alafia, ṣugbọn bi o ba fẹ́ bá ọ jà, njẹ ki iwọ ki o dótì i: 13 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi i lé ọ lọwọ, ki iwọ ki o si fi oju idà pa gbogbo ọkunrin ti mbẹ ninu rẹ̀: 14 Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 15 Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo ilu ti o jìna rére si ọ, ti ki iṣe ninu ilu awọn orilẹ-ède wọnyi. 16 Ṣugbọn ninu ilu awọn enia wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki iwọ ki o máṣe da ohun kan si ti o nmí: 17 Ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn run patapata; awọn ọmọ Hitti, ati awọn Amori, awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: 18 Ki nwọn ki o má ba kọ́ nyin lati ma ṣe bi gbogbo iṣẹ-irira wọn, ti nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; ẹnyin a si ṣẹ̀ bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin. 19 Nigbati iwọ ba dótì ilu kan pẹ titi, lati bá a jà lati kó o, ki iwọ ki o máṣe run igi tutù rẹ̀ ni yiyọ ãke tì wọn; nitoripe iwọ le ma jẹ ninu wọn, iwọ kò si gbọdọ ke wọn lulẹ; nitori igi igbẹ́ ha ṣe enia bi, ti iwọ o ma dòtí i? 20 Kìki igi ti iwọ mọ̀ pe nwọn ki iṣe igi jijẹ, on ni ki iwọ ki o run, ki o si ke lulẹ; ki iwọ ki o si sọ agbàra tì ilu na ti mbá ọ jà, titi a o fi ṣẹ́ ẹ.

Deuteronomi 21

Tí Ikú Ẹnìkan Bá Rúni lójú

1 BI a ba ri ẹnikan ti a pa ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati gbà a, ti o dubulẹ ni igbẹ́, ti a kò si mọ̀ ẹniti o pa a: 2 Nigbana ni ki awọn àgba rẹ ati awọn onidajọ rẹ ki o jade wá, ki nwọn ki o si wọ̀n jijìna awọn ilu ti o yi ẹniti a pa na ká. 3 Yio si ṣe, pe ilu ti o sunmọ ẹniti a pa na, ani awọn àgba ilu na ki nwọn mú ẹgbọrọ abo-malu kan, ti a kò fi ṣiṣẹ rí, ti kò si fà ninu àjaga rí; 4 Ki awọn àgba ilu na ki o mú ẹgbọrọ abo-malu na sọkalẹ wá, si afonifoji ti o ní omi ṣiṣàn kan, ti a kò ro ti a kò si gbìn, ki nwọn ki o si ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abomalu na nibẹ̀ li afonifoji na: 5 Awọn alufa, awọn ọmọ Lefi yio si sunmọtosi; nitoripe awọn ni OLUWA Ọlọrun rẹ yàn lati ma ṣe iṣẹ-ìsin fun u, ati lati ma sure li orukọ OLUWA; nipa ọ̀rọ wọn li a o ti ma wadi ọ̀ran iyàn ati ọ̀ran lilù: 6 Ati gbogbo awọn àgba ilu nì, ti o sunmọ ẹniti a pa na, ki nwọn ki o wẹ̀ ọwọ́ wọn sori ẹgbọrọ abo-malu na, ti a ṣẹ́ li ọrùn li afonifoji nì: 7 Ki nwọn ki o si dahùn wipe, Ọwọ́ wa kò tà ẹ̀jẹ yi silẹ, bẹ̃li oju wa kò ri i. 8 OLUWA, darijì Israeli awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada, ki o má si ṣe kà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ si ọrùn Israeli awọn enia rẹ. A o si dari ẹ̀jẹ na jì wọn. 9 Bẹ̃ni iwọ o si mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lãrin nyin, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.

Àwọn Obinrin Tí Ogun Bá Kó

10 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ si fi wọn lé ọ lọwọ, ti iwọ si dì wọn ni igbekun; 11 Ti iwọ ba si ri ninu awọn igbẹsin na arẹwà obinrin, ti iwọ si ní ifẹ́ si i, pe ki iwọ ki o ní i li aya rẹ; 12 Nigbana ni ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ; ki on ki o si fá ori rẹ̀, ki o si rẹ́ ẽkanna rẹ̀; 13 Ki o si bọ́ aṣọ igbẹsin rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ki o si joko ninu ile rẹ, ki o sọkun baba rẹ̀, ati iya rẹ̀ li oṣù kan tọ̀tọ: lẹhin ìgba na ki iwọ ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ma ṣe ọkọ rẹ̀, on a si ma ṣe aya rẹ. 14 Bi o ba si ṣe, ti on kò ba wù ọ, njẹ ki iwọ ki o jẹ ki o ma lọ si ibi ti o fẹ́; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ tà a rára li owo, iwọ kò gbọdọ lò o bi ẹrú, nitoriti iwọ ti tẹ́ ẹ logo.

Ẹ̀tọ́ Àkọ́bí ninu Ogún Baba Rẹ̀

15 Bi ọkunrin kan ba si lí aya meji, ti o fẹ́ ọkan ti o si korira ekeji, ti nwọn si bi ọmọ fun u, ati eyiti o fẹ́ ati eyiti o korira; bi akọ́bi ọmọ na ba ṣe ti ẹniti o korira; 16 Yio si ṣe, li ọjọ́ ti o ba fi awọn ọmọ rẹ̀ jogún ohun ti o ní, ki o máṣe fi ọmọ obinrin ti o fẹ́ ṣe akọ́bi ni ipò ọmọ obinrin ti o korira, ti iṣe akọ́bi: 17 Ṣugbọn ki o jẹwọ ọmọ obinrin ti o korira li akọ́bi, ni fifi ipín meji fun u ninu ohun gbogbo ti o ní: nitoripe on ni ipilẹṣẹ agbara rẹ̀; itọsi akọ́bi ni tirẹ̀.

Bí Ọmọ Ẹni Bá Ya Aláìgbọràn

18 Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́: 19 Nigbana ni ki baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ki o mú u, ki nwọn ki o si fà a jade tọ̀ awọn àgba ilu rẹ̀ wá ati si ibode ibujoko rẹ̀; 20 Ki nwọn ki o si wi fun awọn àgba ilu rẹ̀ pe, Ọmọ wa yi, alagídi ati alaigbọran ni, on kò fẹ́ gbọ́ ohùn wa; ọjẹun ati ọmuti ni. 21 Ki gbogbo awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-ibi kuro lãrin nyin; gbogbo Israeli a si gbọ́, nwọn a si bẹ̀ru.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

22 Bi ọkunrin kan ba dá ẹ̀ṣẹ kan ti o yẹ si ikú, ti a si pa a, ti iwọ si so o lori igi; 23 Ki okú rẹ̀ ki o máṣe gbé ori igi ni gbogbo oru, ṣugbọn bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o sin i li ọjọ́ na; nitoripe ẹni egún Ọlọrun li ẹniti a so; ki iwọ ki o má ba bà ilẹ rẹ jẹ́, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.

Deuteronomi 22

1 IWỌ kò gbọdọ ri akọ-malu tabi agutan arakunrin rẹ ti o nṣako, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn; bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o mú wọn pada tọ̀ arakunrin rẹ wá. 2 Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada. 3 Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro. 4 Iwọ kò gbọdọ ri kẹtẹkẹtẹ tabi akọ-malu arakunrin rẹ ki o ṣubu li ọ̀na, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn: iwọ o si ràn a lọwọ nitõtọ lati gbé e dide. 5 Obinrin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ̀, bẹ̃li ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bẹ̃ irira ni nwọn si OLUWA Ọlọrun rẹ. 6 Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ: 7 Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ. 8 Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu. 9 Iwọ kò gbọdọ fi irú meji irugbìn gbìn ọgbà-àjara rẹ; ki eso irugbìn rẹ gbogbo ti iwọ ti gbìn, ati asunkún ọgbà-àjara rẹ, ki o má ba di ti Ọlọrun. 10 Iwọ kò gbọdọ fi akọ-malu ati kẹtẹkẹtẹ tulẹ pọ̀. 11 Iwọ kò gbọdọ wọ̀ aṣọ olori-ori, ti kubusu ati ti ọ̀gbọ pọ̀. 12 Ki iwọ ki o ṣe wajawaja si igun mẹrẹrin aṣọ rẹ, ti iwọ fi mbò ara rẹ.

Òfin nípa Ìbálòpọ̀ Ọkunrin ati Obinrin

13 Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo kan, ti o wọle tọ̀ ọ, ti o si korira rẹ̀, 14 Ti o si kà ọ̀ran si i lọrùn, ti o si bà orukọ rẹ̀ jẹ́, ti o si wipe, Mo gbé obinrin yi, nigbati mo si wọle tọ̀ ọ, emi kò bá a ni wundia: 15 Nigbana ni ki baba ọmọbinrin na, ati iya rẹ̀, ki o mú àmi wundia ọmọbinrin na tọ̀ awọn àgba ilu lọ li ẹnu-bode: 16 Ki baba ọmọbinrin na ki o si wi fun awọn àgba na pe, Emi fi ọmọbinrin mi fun ọkunrin yi li aya, o si korira rẹ̀; 17 Si kiyesi i, o si kà ọ̀ran si i lọrùn, wipe, Emi kò bá ọmọbinrin rẹ ni wundia; bẹ̃ni wọnyi ni àmi wundia ọmọbinrin mi. Ki nwọn ki o si nà aṣọ na niwaju awọn àgba ilu. 18 Ki awọn àgba ilu na ki o si mú ọkunrin na ki nwọn ki o si nà a; 19 Ki nwọn ki o si bù ọgọrun ṣekeli fadakà fun u, ki nwọn ki o si fi i fun baba ọmọbinrin na, nitoriti o bà orukọ wundia kan ni Israeli jẹ́: ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀; ki o máṣe kọ̀ ọ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo. 20 Ṣugbọn bi ohun na ba ṣe otitọ, ti a kò ba si ri àmi wundia ọmọbinrin na: 21 Nigbana ni ki nwọn ki o mú ọmọbinrin na wá si ẹnu-ọ̀na ile baba rẹ̀, ki awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: nitoriti o hù ìwa-buburu ni Israeli, ni ṣiṣe àgbere ninu ile baba rẹ̀: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin. 22 Bi a ba mú ọkunrin kan ti o bá obinrin kan dàpọ, ti a gbé ni iyawo fun ọkọ, njẹ ki awọn mejeji ki o kú, ati ọkunrin ti o bá obinrin na dàpo, ati obinrin na: bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ìwa-buburu kuro ni Israeli. 23 Bi ọmọbinrin wundia kan ba wà ni afẹsọna fun ọkọ, ti ọkunrin kan si ri i ni ilu, ti o si bá a dàpọ; 24 Njẹ ki ẹnyin ki o mú awọn mejeji wá si ẹnu-bode ilu na, ki ẹnyin ki o si ṣo wọn li okuta pa; eyi ọmọbinrin nitoriti kò kigbe, nigbati o wà ni ilu; ati eyi ọkunrin nitoriti o tẹ́ aya ẹnikeji rẹ̀ logo: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin. 25 Ṣugbọn bi ọkunrin na ba ri ọmọbinrin ti afẹsọna na ni igbẹ́, ti ọkunrin na si fi agbara mú u, ti o si bà a dàpọ; njẹ kìki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ni ki o kú: 26 Ṣugbọn si ọmọbinrin na ni ki iwọ ki o máṣe ohun kan; ẹ̀ṣẹ ti o yẹ si ikú kò sí lara ọmọbinrin na: nitori bi igbati ọkunrin kan dide si ẹnikeji rẹ̀, ti o si pa a, bẹ̃li ọ̀ran yi ri: 27 Nitoripe o bá a ninu igbẹ́; ọmọbinrin na ti afẹsọna kigbe, kò si sí ẹniti yio gbà a silẹ. 28 Bi ọkunrin kan ba si ri ọmọbinrin kan ti iṣe wundia, ti a kò ti fẹsọna fun ọkọ, ti o si mú u, ti o si bá a dàpọ, ti a si mú wọn; 29 Njẹ ki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ki o fi ãdọta ṣekeli fadakà fun baba ọmọbinrin na, ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀, nitoriti o ti tẹ́ ẹ logo, ki on ki o máṣe kọ̀ ọ silẹ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo. 30 Ki ọkunrin kan ki o máṣe fẹ́ aya baba rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe tú aṣọ baba rẹ̀.

Deuteronomi 23

Yíyọ Orúkọ Eniyan kúrò ninu Orúkọ Àwọn Eniyan OLUWA

1 ẸNITI a fọ ni kóro, tabi ti a ke ẹ̀ya ìkọkọ rẹ̀ kuro, ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA. 2 Ọmọ-àle ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia rẹ̀ kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA. 3 Ọmọ Ammoni tabi ọmọ Moabu kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia wọn kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA lailai: 4 Nitoriti nwọn kò fi omi pẹlu onjẹ pade nyin li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti Egipti jade wá; ati nitoriti nwọn bẹ̀wẹ Balaamu ọmọ Beori ara Petori ti Mesopotamia si ọ, lati fi ọ bú. 5 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; OLUWA Ọlọrun rẹ si yi egún na pada si ibukún fun ọ, nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ fẹ́ ọ. 6 Iwọ kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn li ọjọ́ rẹ gbogbo lailai. 7 Iwọ kò gbọdọ korira ara Edomu kan; nitoripe arakunrin rẹ ni iṣe: iwọ kò gbọdọ korira ara Egipti kan; nitoripe iwọ ti ṣe alejò ni ilẹ rẹ̀. 8 Awọn ọmọ ti a bi fun wọn yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA ni iran kẹta wọn.

Jíjẹ́ Kí Àgọ́ Àwọn Ọmọ-ogun Wà ní Mímọ́

9 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o pa ara rẹ mọ́ kuro ninu ohun buburu gbogbo. 10 Bi ọkunrin kan ba wà ninu nyin, ti o ṣèsi di aimọ́ li oru, njẹ ki o jade lọ sẹhin ibudó, ki o máṣe wá ãrin ibudó: 11 Yio si ṣe, nigbati alẹ ba lẹ, ki on ki o fi omi wẹ̀ ara rẹ̀: nigbati õrùn ba si wọ̀, ki o ma bọ̀wá sãrin ibudó. 12 Ki iwọ ki o ní ibi kan pẹlu lẹhin ibudó, nibiti iwọ o ma jade lọ si: 13 Ki iwọ ki o si ní ìwalẹ kan pẹlu ohun-ìja rẹ; yio si ṣe, nigbati iwọ o ba gbọnsẹ lẹhin ibudó, ki iwọ ki o fi wàlẹ, ki iwọ ki o si yipada, ki o bò ohun ti o ti ara rẹ jade: 14 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ nrìn lãrin ibudó rẹ, lati gbà ọ, ati lati fi awọn ọtá rẹ fun ọ; nitorina ki ibudó rẹ ki o jẹ́ mimọ́: ki on ki o máṣe ri ohun aimọ́ kan lọdọ rẹ, on a si pada lẹhin rẹ.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

15 Iwọ kò gbọdọ fà ẹrú ti o sá lati ọdọ oluwa rẹ̀ tọ̀ ọ wá lé oluwa rẹ̀ lọwọ: 16 Ki on ki o bá ọ joko, ani lãrin nyin, ni ibi ti on o yàn ninu ọkan ni ibode rẹ, ti o wù u jù: ki iwọ ki o máṣe ni i lara. 17 Ki àgbere ki o máṣe sí ninu awọn ọmọbinrin Israeli, tabi oníwà-sodomu ninu awọn ọmọkunrin Israeli. 18 Iwọ kò gbọdọ mú owo ọ̀ya àgbere, tabi owo ajá, wá sinu ile OLUWA Ọlọrun rẹ fun ẹjẹ́kẹjẹ: nitoripe irira ni, ani awọn mejeji si OLUWA Ọlọrun rẹ. 19 Iwọ kò gbọdọ wín arakunrin rẹ fun elé; elé owo, elé onjẹ, elé ohun kan ti a wínni li elé: 20 Alejò ni ki iwọ ki o ma wín fun elé; ṣugbọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o máṣe win fun elé: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma bukún ọ ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé, ni ilẹ na nibiti iwọ nlọ lati gbà a. 21 Nigbati iwọ ba jẹ́jẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rẹ̀ nitõtọ lọwọ rẹ; yio si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn. 22 Ṣugbọn bi iwọ ba fàsẹhin lati jẹ́jẹ, ki yio di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn. 23 Ohun ti o ba ti ète rẹ jade, ni ki iwọ ki o pamọ́, ki o si ṣe; gẹgẹ bi iwọ ti jẹ́jẹ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ani ọrẹ ifẹ́-atinuwa, ti iwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ileri. 24 Nigbati iwọ ba wọ̀ inu ọgbà-àjara ẹnikeji rẹ lọ, iwọ le jẹ eso-àjara tẹrùn; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ mú ọkan sinu ohunèlo rẹ. 25 Nigbati iwọ ba dé inu oko-ọkà ẹnikeji rẹ, njẹ ki iwọ ki o ma fi ọwọ́ rẹ yà ṣiri rẹ̀; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ yọ doje si ọkà ẹnikeji rẹ.

Deuteronomi 24

Kíkọ Iyawo sílẹ̀ ati Títún Igbeyawo ṣe

1 BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀. 2 Nigbati on ba si jade kuro ninu ile rẹ̀, on le lọ, ki o ma ṣe aya ọkunrin miran. 3 Bi ọkọ rẹ̀ ikẹhin ba si korira rẹ̀, ti o si kọ iwé ikọsilẹ fun u, ti o si fi i lé e lọwọ, ti o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀; tabi bi ọkọ ikẹhin ti o fẹ́ ẹ li aya ba kú; 4 Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

5 Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn. 6 Ẹnikan kò gbọdọ gbà iya-ọ̀lọ tabi ọmọ-ọlọ ni ògo: nitoripe ẹmi enia li o gbà li ògo nì. 7 Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin. 8 Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe. 9 Ranti ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Miriamu li ọ̀na, nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá. 10 Nigbati iwọ ba wín arakunrin rẹ li ohun kan, ki iwọ ki o máṣe lọ si ile rẹ̀ lati mú ògo rẹ̀ wá. 11 Ki iwọ ki o duro lode gbangba, ki ọkunrin na ti iwọ wín ni nkan, ki o mú ògo rẹ̀ jade tọ̀ ọ wá. 12 Bi ọkunrin na ba si ṣe talakà, ki iwọ ki o máṣe sùn ti iwọ ti ògo rẹ̀. 13 Bi o ti wù ki o ri iwọ kò gbọdọ má mú ògo rẹ̀ pada fun u, nigbati õrùn ba nwọ̀, ki on ki o le ri aṣọ bora sùn, ki o si sure fun ọ: ododo ni yio si jasi fun ọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ. 14 Iwọ kò gbọdọ ni alagbaṣe kan lara ti iṣe talakà ati alaini, ibaṣe ninu awọn arakunrin rẹ, tabi ninu awọn alejò rẹ ti mbẹ ni ilẹ rẹ ninu ibode rẹ: 15 Ni ọjọ́ rẹ̀, ni ki iwọ ki o sanwo ọ̀ya rẹ̀ fun u, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki õrùn ki o wọ̀ bá a; nitoripe talakà li on, o si gbẹkẹ rẹ̀ lé e: ki o má ba kepè OLUWA si ọ, a si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn. 16 A kò gbọdọ pa awọn baba nitori ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 17 Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò: 18 Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni Egipti, OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ kuro nibẹ̀: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi. 19 Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo. 20 Nigbati iwọ ba ngún igi olifi rẹ, ki iwọ ki o máṣe tun pada wò ẹka rẹ̀: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó. 21 Nigbati iwọ ba nká eso ọgbà-àjara rẹ, ki iwọ ki o máṣe peṣẹ́ lẹhin rẹ: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó. 22 Ki iwọ ki o si ma ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.

Deuteronomi 25

1 BI gbolohùn-asọ̀ kan ba wà lãrin enia, ti nwọn si wá si ibi idajọ, ti nwọn si dajọ wọn; nigbana ni ki nwọn ki o fi are fun alare, ki nwọn ki o si fi ẹbi fun ẹlẹbi; 2 Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀. 3 Ogoji paṣan ni ki a nà a, kò gbọdọ lé: nitoripe bi o ba lé, ti o ba si fi paṣan pupọ̀ nà a jù wọnyi lọ, njẹ arakunrin rẹ yio di gigàn li oju rẹ. 4 Máṣe di akọ-malu li ẹnu nigbati o ba npakà.

Ojúṣe Ẹni sí Arakunrin Ẹni Tí Ó Ṣaláìsí

5 Bi awọn arakunrin ba ngbé pọ̀, ti ọkan ninu wọn ba si kú, ti kò si lí ọmọkunrin, ki aya okú ki o máṣe ní alejò ara ode li ọkọ: arakunrin ọkọ rẹ ni ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ní i li aya, ki o si ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ fun u. 6 Yio si ṣe, akọ́bi ọmọ ti o bi ki o rọpò li orukọ arakunrin rẹ̀ ti o kú, ki orukọ rẹ̀ ki o má ba parẹ́ ni Israeli. 7 Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi. 8 Nigbana ni awọn àgba ilu rẹ̀ yio pè e, nwọn a si sọ fun u: bi o ba si duro si i, ti o si wipe, Emi kò fẹ́ lati mú u; 9 Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀. 10 A o si ma pè orukọ rẹ̀ ni Israeli pe, Ile ẹniti a tú bàta rẹ̀.

Àwọn Òfin Mìíràn

11 Bi awọn ọkunrin ba mbá ara wọn jà, ti aya ọkan ba si sunmọtosi lati gbà ọkọ rẹ̀ lọwọ ẹniti o kọlù u, ti on si nawọ́ rẹ̀, ti o si di i mú li abẹ: 12 Nigbana ni ki iwọ ki o ke ọwọ́ rẹ̀ kuro, ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u. 13 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru ìwọn ninu àpo rẹ, nla ati kekere. 14 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru òṣuwọn ninu ile rẹ, nla ati kekere. 15 Iwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní; òṣuwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 16 Nitoripe gbogbo ẹniti nṣe wọnyi, ati gbogbo ẹniti nṣe aiṣododo, irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.

Òfin láti Pa Àwọn Ará Amaleki

17 Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá; 18 Bi o ti pade rẹ li ọ̀na, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ãrẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bẹ̀ru Ọlọrun. 19 Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki rẹ́ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé.

Deuteronomi 26

Ọrẹ Ìkórè

1 YIO si ṣe, nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ti iwọ si gbà a, ti iwọ si joko ninu rẹ̀; 2 Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si. 3 Ki iwọ ki o si tọ̀ alufa na lọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni, ki o si wi fun u pe, Emi jẹwọ li oni fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pe emi wá si ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba wa lati fi fun wa. 4 Ki awọn alufa ki o si gbà agbọ̀n na li ọwọ́ rẹ, ki o si gbé e kalẹ niwaju pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ. 5 Iwọ o si dahùn iwọ o si wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Ara Siria kan, ti o nṣegbé ni baba mi, on si sọkalẹ lọ si Egipti, o si ṣe atipo nibẹ̀, ti on ti enia diẹ; nibẹ̀ li o si di orilẹ-ède nla, alagbara, ati pupọ̀: 6 Awọn ara Egipti si hùwabuburu si wa, nwọn si pọn wa loju, nwọn si dì ẹrù wuwo rù wa: 7 Awa si kepè OLUWA, Ọlọrun awọn baba wa, OLUWA si gbọ́ ohùn wa, o si wò ipọnju wa, ati lãlã wa, ati inira wa: 8 OLUWA si mú wa lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara, ati apa ninà, ati pẹlu ẹrù nla, ati pẹlu iṣẹ-àmi, ati pẹlu iṣẹ-iyanu: 9 O si mú wa dé ihin yi, o si fi ilẹ yi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, emi mú akọ́so ilẹ na wa, ti iwọ, OLUWA, fi fun mi. Ki iwọ ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma foribalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ: 11 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ohun rere gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ati fun ara ile rẹ, iwọ, ati ọmọ Lefi, ati alejò ti mbẹ lãrin rẹ. 12 Nigbati iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tán li ọdún kẹta, ti iṣe ọdún idamẹwa, ti iwọ si fi fun ọmọ Lefi, alejò, alainibaba, ati opó, ki nwọn ki o ma jẹ li ẹnubode rẹ, ki nwọn si yó; 13 Nigbana ni ki iwọ ki o wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mú ohun mimọ́ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejò, ati fun alainibaba, ati fun opó, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi kò re aṣẹ rẹ kọja, bẹ̃li emi kò gbagbé wọn: 14 Emi kò jẹ ninu rẹ̀ ninu ọ̀fọ mi, bẹ̃li emi kò mú kuro ninu rẹ̀ fun ohun aimọ́ kan, bẹ̃li emi kò mú ninu rẹ̀ fun okú: ṣugbọn emi ti gbà ohùn OLUWA Ọlọrun mi gbọ́, emi si ti ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ palaṣẹ fun mi. 15 Wò ilẹ lati ibujoko mimọ́ rẹ wá, lati ọrun wá, ki o si busi i fun Israeli enia rẹ, ati fun ilẹ na ti iwọ fi fun wa, bi iwọ ti bura fun awọn baba wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

Àwọn Eniyan OLUWA

16 Li oni OLUWA Ọlọrun rẹ paṣẹ fun ọ lati ma ṣe ìlana ati idajọ wọnyi: nitorina ki iwọ ki o ma pa wọn mọ́, ki iwọ ki o si ma fi gbogbo àiya rẹ ati gbogbo ọkàn rẹ ṣe wọn. 17 Iwọ jẹwọ OLUWA li oni pe on ni Ọlọrun rẹ, ati pe iwọ o ma rìn li ọ̀na rẹ̀, iwọ o si ma pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, iwọ o si ma fetisi ohùn rẹ̀: 18 OLUWA si jẹwọ rẹ li oni pe iwọ o ma jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ati pe iwọ o ma pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́; 19 On o si mu ọ ga jù orilẹ-ède gbogbo lọ ti o dá, ni ìyin, li orukọ, ati ọlá; ki iwọ ki o le ma jẹ́ enia mimọ́ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ.

Deuteronomi 27

Ìlànà nípa Kíkọ Òfin Ọlọrun Sára Òkúta

1 MOSE pẹlu awọn àgba Israeli si paṣẹ fun awọn enia na wipe, Ẹ ma pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni. 2 Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn. 3 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ. 4 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani tán, ẹnyin o kó okuta wọnyi jọ, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, li òke Ebali, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn. 5 Nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pẹpẹ okuta kan: iwọ kò gbọdọ fi ohun-èlo irin kàn wọn. 6 Okuta aigbẹ́ ni ki iwọ ki o fi mọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA Ọlọrun rẹ: 7 Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ alafia, ki iwọ ki o si jẹun nibẹ̀; ki iwọ ki o ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ. 8 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara okuta wọnyi, ki o hàn gbangba. 9 Mose ati awọn alufa awọn ọmọ Lefi si sọ fun gbogbo Israeli pe, Israeli, dakẹ, ki o si gbọ́; li oni ni iwọ di enia OLUWA Ọlọrun rẹ. 10 Nitorina ki iwọ ki o gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, ki o si ma ṣe aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.

Àwọn Ègún fún Àìgbọràn

11 Mose si paṣẹ fun awọn enia na li ọjọ́ na, wipe, 12 Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini: 13 Awọn wọnyi ni yio si duro lori òke Ebali lati gegún; Reubeni, Gadi, ati Aṣeri, ati Sebuluni, Dani, ati Naftali. 14 Awọn ọmọ Lefi yio si dahùn, nwọn o si wi fun gbogbo awọn ọkunrin Israeli li ohùn rara pe, 15 Egún ni fun ọkunrin na ti o yá ere gbigbẹ́ tabi didà, irira si OLUWA, iṣẹ ọwọ́ oniṣọnà, ti o si gbé e kalẹ ni ìkọ̀kọ̀. Gbogbo enia yio si dahùn wipe, Amin. 16 Egún ni fun ẹniti kò fi baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀ pè. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 17 Egún ni fun ẹniti o ṣí àla ẹnikeji rẹ̀ kuro. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 18 Egún ni fun ẹniti o ṣì afọju li ọ̀na. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 19 Egún ni fun ẹniti o nyi idajọ alejò po, ati ti alainibaba, ati ti opó. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 20 Egún ni fun ẹniti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ̀: nitoriti o tú aṣọ baba rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 21 Egún ni fun ẹniti o bá ẹranko dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 22 Egún ni fun ẹniti o bá arabinrin rẹ̀ dàpọ, ti iṣe ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 23 Egún ni fun ẹniti o bá iya-aya rẹ̀ dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 24 Egún ni fun ẹniti o lù ẹnikeji rẹ̀ ni ìkọkọ. Gbogbo enia ni yio si wipe, Amin. 25 Egún ni fun ẹniti o gbà ọrẹ lati pa alaiṣẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin. 26 Egún ni fun ẹniti kò duro si gbogbo ọ̀rọ ofin yi lati ṣe wọn. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.

Deuteronomi 28

Ibukun fún Ìgbọràn

1 YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ: 2 Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ. 3 Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko. 4 Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ. 5 Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ. 6 Ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba jade. 7 OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje. 8 OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. 9 OLUWA yio fi idi rẹ kalẹ li enia mimọ́ fun ara rẹ̀, bi o ti bura fun ọ, bi iwọ ba pa aṣẹ ỌLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, ti iwọ si rìn li ọ̀na rẹ̀. 10 Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npè ọ; nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ. 11 OLUWA yio si sọ ọ di pupọ̀ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu irú ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ilẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ. 12 OLUWA yio ṣí iṣura rere rẹ̀ silẹ fun ọ, ọrun lati rọ̀jo si ilẹ rẹ li akokò rẹ̀, ati lati busi iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: iwọ o si ma wín orilẹ-ède pupọ̀, iwọ ki yio si tọrọ. 13 OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe ìru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jẹ́ ẹni ẹhin; bi o ba fetisi aṣẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ li oni, lati ma kiyesi on ati ma ṣe wọn; 14 Iwọ kò si gbọdọ yà kuro ninu gbogbo ọ̀rọ ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, si ọtún, tabi si òsi, lati tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn.

Ìjìyà fún Àìgbọràn

15 Yio si ṣe, bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ ti mo filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ. 16 Egún ni fun ọ ni ilu, egún ni fun ọ li oko. 17 Egún ni fun agbọ̀n rẹ ati ọpọ́n-ipò-àkara rẹ. 18 Egún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ. 19 Egún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, egún si ni fun ọ nigbati iwọ ba jade. 20 OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ. 21 OLUWA yio si mu ajakalẹ-àrun lẹ̀ mọ́ ọ, titi on o fi run ọ kuro lori ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. 22 OLUWA yio si fi àrun-igbẹ kọlù ọ, ati ibà, ati igbona, ati ijoni nla, ati idà, ati ìrẹdanu, ati imuwodu; nwọn o si lepa rẹ titi iwọ o fi run. 23 Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jẹ́ idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio si jẹ́ irin. 24 OLUWA yio sọ òjo ilẹ rẹ di ẹ̀tù ati ekuru: lati ọrun ni yio ti ma sọkalẹ si ọ, titi iwọ o fi run. 25 OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ̀ wọn lọ li ọ̀na kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọ̀na meje: a o si ṣí ọ kiri gbogbo ijọba aiye. 26 Okú rẹ yio si jẹ́ onjẹ fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọ̀run, ati fun ẹranko aiye, kò si sí ẹniti yio lé wọn kuro. 27 OLUWA yio si fi õwo Egipti lù ọ, ati iyọdi, ati ekúru, ati ẹyi-ara, eyiti a ki yio le wòsan. 28 OLUWA yio fi isinwin kọlù ọ, ati ifọju, ati ipàiya: 29 Iwọ o si ma fi ọwọ́ talẹ li ọsán gangan, bi afọju ti ifi ọwọ́ talẹ ninu òkunkun, iwọ ki yio si ri rere ninu ọ̀na rẹ: ẹni inilara ṣá ati ẹni kikó li ọjọ́ gbogbo ni iwọ o jẹ́, ki o si sí ẹniti o gbà ọ. 30 Iwọ o fẹ́ iyawo, ọkunrin miran ni yio si bá a dàpọ: iwọ o kọ ile, iwọ ki yio si gbé inu rẹ̀: iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ ki yio si ká eso rẹ̀. 31 A o si pa akọmalu rẹ li oju rẹ, iwọ ki yio si jẹ ninu rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ rẹ li a o si fi agbara mú lọ kuro li oju rẹ, a ki yio si mú u pada fun ọ wá: a o fi agutan rẹ fun awọn ọtá rẹ, iwọ ki yio si lí ẹniti yio gbà ọ. 32 Awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, li a o fi fun enia miran, oju rẹ yio ma wò, yio si su ọ lati ma wò ọ̀na wọn li ọjọ́ gbogbo: ki yio si sí agbara kan li ọwọ́ rẹ. 33 Eso ilẹ rẹ, ati gbogbo iṣẹ-lãlã rẹ, ni orilẹ-ède miran ti iwọ kò mọ̀ yio jẹ; iwọ o si jẹ́ kìki ẹni inilara ati ẹni itẹmọlẹ nigbagbogbo: 34 Bẹ̃ni iwọ o si di aṣiwere nitori iran oju rẹ, ti iwọ o ri. 35 OLUWA yio si fi õwo buburu lù ọ li ẽkún, ati li ẹsẹ̀, ti a ki o le wòsan, lati atẹlẹsẹ̀ rẹ dé atari rẹ. 36 OLUWA o mú iwọ, ati ọba rẹ ti iwọ o fi jẹ́ lori rẹ, lọ si orilẹ-ède ti iwọ, ati awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; iwọ o si ma bọ oriṣa nibẹ̀, igi ati okuta. 37 Iwọ o si di ẹni iyanu, ati ẹni owe, ati ẹni ifisọrọsọ, ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio gbé darí rẹ si. 38 Iwọ o mú irugbìn pupọ̀ lọ sinu oko, diẹ ni iwọ o si ri kójọ; nitoripe eṣú ni yio jẹ ẹ run. 39 Iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ o si ṣe itọju rẹ̀, ṣugbọn iwọ ki yio mu ninu ọti-waini rẹ̀, bẹ̃ni iwọ ki yio ká ninu eso-àjara rẹ̀, nitoripe kòkoro ni yio fi wọn jẹ. 40 Iwọ o ní igi olifi ni gbogbo àgbegbe rẹ, ṣugbọn iwọ ki yio fi oróro para; nitoripe igi olifi rẹ yio rẹ̀danu. 41 Iwọ o bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn nwọn ki yio jẹ́ tirẹ; nitoripe nwọn o lọ si oko-ẹrú. 42 Gbogbo igi rẹ ati eso ilẹ rẹ yio jẹ́ ti eṣú. 43 Alejò ti mbẹ lãrin rẹ, yio ma ga jù ọ lọ siwaju ati siwaju, iwọ o si ma di ẹni irẹsilẹ, siwaju ati siwaju. 44 On ni yio ma wín ọ, iwọ ki yio si wín i: on ni yio ma ṣe ori, iwọ o si ma ṣe ìru. 45 Gbogbo egún wọnyi yio si wá sori rẹ, yio si lepa rẹ, yio si bá ọ, titi iwọ o fi run; nitoriti iwọ kò fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́ ti o palaṣe fun ọ. 46 Nwọn o si wà lori rẹ fun àmi ati fun iyanu, ati lori irú-ọmọ rẹ lailai: 47 Nitoriti iwọ kò fi àyọ sìn OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inudidun, nitori ọ̀pọ ohun gbogbo: 48 Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ. 49 OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀; 50 Orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojuṣaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe: 51 On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ. 52 On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ. 53 Iwọ o si jẹ ọmọ inu rẹ, ẹran ara awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ninu idótì na ati ninu ihámọ na ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́. 54 Ọkunrin ti àwọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, oju rẹ̀ yio korò si arakunrin rẹ̀, ati si aya õkanàiya rẹ̀, ati si iyokù ọmọ rẹ̀ ti on jẹ kù: 55 Tobẹ̃ ti on ki yio bùn ẹnikan ninu wọn, ninu ẹran awọn ọmọ ara rẹ̀ ti o jẹ, nitoriti kò sí ohun kan ti yio kù silẹ fun u ninu idótì na ati ninu ihámọ, ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ gbogbo. 56 Obinrin ti awọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, ti kò jẹ daṣa ati fi atẹlẹsẹ̀ rẹ̀ kan ilẹ nitori ikẹra ati ìwa-ẹlẹgẹ́, oju rẹ̀ yio korò si ọkọ õkanaiya rẹ̀, ati si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin; 57 Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ. 58 Bi iwọ kò ba fẹ́ kiyesi ati ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi ti a kọ sinu iwé yi, lati ma bẹrù orukọ yi ti o lí ogo ti o si lí ẹ̀ru OLUWA ỌLỌRUN RẸ; 59 Njẹ OLUWA yio sọ iyọnu rẹ di iyanu, ati iyọnu irú-ọmọ rẹ, ani iyọnu nla, ati eyiti yio pẹ, ati àrun buburu, ati eyiti yio pẹ. 60 On o si mú gbogbo àrun Egipti pada wá bá ọ, ti iwọ bẹ̀ru; nwọn o si lẹ̀ mọ́ ọ. 61 Gbogbo àrun pẹlu, ati gbogbo iyọnu, ti a kò kọ sinu iwé ofin yi, awọn ni OLUWA yio múwa bá ọ, titi iwọ o fi run. 62 Diẹ li ẹnyin o si kù ni iye, ẹnyin ti ẹ ti dabi irawọ oju-ọrun ni ọ̀pọlọpọ: nitoriti iwọ kò gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́. 63 Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ̀ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ̀; bẹ̃ni OLUWA yio si yọ̀ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a. 64 OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ̀ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ̀ rí, ani igi ati okuta. 65 Ati lãrin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹ̃li atẹlẹsẹ̀ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, ati oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ: 66 Ẹmi rẹ yio sọrọ̀ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹ̀ru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ní idaniloju ẹmi rẹ. 67 Li owurọ̀ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ́ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ́ mọ́! nitori ibẹ̀ru àiya rẹ ti iwọ o ma bẹ̀ru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri. 68 OLUWA yio si fi ọkọ̀ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọ̀na ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ́: nibẹ̀ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkunrin ati ẹrú obinrin, ki yio si sí ẹniti yio rà nyin.

Deuteronomi 29

Àdéhùn OLUWA pẹlu Israẹli ní Ilẹ̀ Moabu

1 WỌNYI li ọ̀rọ majẹmu ti OLUWA palaṣẹ fun Mose lati bá awọn ọmọ Israeli dá ni ilẹ Moabu, lẹhin majẹmu ti o ti bá wọn dá ni Horebu. 2 Mose si pè gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ri ohun gbogbo ti OLUWA ṣe li oju nyin ni ilẹ Egipti si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ati si ilẹ rẹ̀ gbogbo. 3 Idanwò nla ti oju rẹ ti ri, iṣẹ-àmi, ati iṣẹ-iyanu nla wọnni: 4 Ṣugbọn OLUWA kò fun nyin li àiya lati mọ̀, ati oju lati ri, ati etí lati gbọ́ titi di oni yi. 5 Emi si ti mu nyin rìn li ogoji ọdún li aginjù: aṣọ nyin kò gbó mọ́ nyin li ara, bàta nyin kò si gbó mọ́ nyin ni ẹsẹ̀. 6 Ẹnyin kò jẹ àkara, bẹ̃li ẹnyin kò mu ọti-waini, tabi ọti lile: ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 7 Nigbati ẹnyin ti dé ihinyi, Sihoni ọba Hesboni, ati Ogu ọba Baṣani, jade ogun si wa, awa si kọlù wọn: 8 Awa si gbà ilẹ wọn, a si fi i fun awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse ni iní. 9 Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe. 10 Gbogbo nyin li o duro li oni niwaju OLUWA Ọlọrun nyin; awọn olori nyin, awọn ẹ̀ya nyin, awọn àgba nyin, ati awọn ijoye nyin, ani gbogbo awọn ọkunrin Israeli, 11 Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ: 12 Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni: 13 Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu. 14 Ki si iṣe ẹnyin nikan ni mo bá ṣe majẹmu yi ati ibura yi; 15 Ṣugbọn ẹniti o bá wa duro nihin li oni niwaju OLUWA Ọlọrun wa, ẹniti kò sí nihin pẹlu wa li oni: 16 (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja; 17 Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.) 18 Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin; 19 Yio si ṣe, nigbati o ba gbọ́ ọ̀rọ egún yi, ti o sure fun ara rẹ̀ ninu àiya rẹ̀, wipe, Emi o ní alafia, bi emi tilẹ nrìn ninu agídi ọkàn mi, lati run tutù pẹlu gbigbẹ: 20 OLUWA ki yio darijì i, ṣugbọn nigbana ni ibinu OLUWA ati owú rẹ̀ yio gbona si ọkunrin na, ati gbogbo egún wọnyi ti a kọ sinu iwé yi ni yio bà lé e, OLUWA yio si nù orukọ rẹ̀ kuro labẹ ọrun. 21 OLUWA yio si yà a si ibi kuro ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, gẹgẹ bi gbogbo egún majẹmu, ti a kọ sinu iwé ofin yi. 22 Ati iran ti mbọ̀, awọn ọmọ nyin ti yio dide lẹhin nyin, ati alejò ti yio ti ilẹ jijìn wá, yio si wi, nigbati nwọn ba ri iyọnu ilẹ na, ati àrun na, ti OLUWA mu bá a; 23 Ati pe gbogbo ilẹ rẹ̀ di imi-õrùn, ati iyọ̀, ati ijóna, ti a kò le gbìn nkan si, tabi ti kò le seso, tabi ti koriko kò le hù ninu rẹ̀, bi ibìṣubu Sodomu, ati Gomorra, Adma, ati Seboiimu, ti OLUWA bìṣubu ninu ibinu rẹ̀, ati ninu ikannu rẹ̀: 24 Ani gbogbo orilẹ-ède yio ma wipe, Ẽṣe ti OLUWA fi ṣe bayi si ilẹ yi? Kili a le mọ̀ õru ibinu nla yi si? 25 Nwọn o si wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ majẹmu OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o ti bá wọn dá nigbati o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá. 26 Nitoriti nwọn lọ, nwọn si bọ oriṣa, nwọn si tẹriba fun wọn, oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, ti on kò si fi fun wọn. 27 Ibinu OLUWA si rú si ilẹ na, lati mú gbogbo egún ti a kọ sinu iwé yi wá sori rẹ̀: 28 OLUWA si fà wọn tu kuro ni ilẹ wọn ni ibinu, ati ni ikannu, ati ni irunu nla, o si lé wọn lọ si ilẹ miran, bi o ti ri li oni yi. 29 Ti OLUWA Ọlọrun wa ni ohun ìkọkọ: ṣugbọn ohun ti afihàn ni tiwa ati ti awọn ọmọ wa lailai, ki awa ki o le ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.

Deuteronomi 30

Ìpadà-bọ̀-sípò ati Ibukun Israẹli

1 YIO si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ o ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si, 2 Ti iwọ ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo; 3 Nigbana ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio yi oko-ẹrú rẹ pada, yio si ṣãnu fun ọ, yio si pada, yio si kó ọ jọ kuro ninu gbogbo orilẹ-ède wọnni nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si. 4 Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si ìha opin ọrun, lati ibẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ̀ ni yio si mú ọ wá: 5 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si mú ọ wá sinu ilẹ na ti awọn baba rẹ ti ní, iwọ o si ní i; on o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bisi i jù awọn baba rẹ lọ. 6 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè. 7 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si fi gbogbo egún wọnyi lé awọn ọtá rẹ lori, ati lori awọn ti o korira rẹ, ti nṣe inunibini si ọ. 8 Iwọ o si pada, iwọ o si gbà ohùn OLUWA gbọ́, iwọ o si ma ṣe gbogbo ofin rẹ̀ ti mo palaṣẹ fun ọ li oni. 9 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si sọ ọ di pupọ̀ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, fun rere: nitoriti OLUWA yio pada wa yọ̀ sori rẹ fun rere, bi o ti yọ̀ sori awọn baba rẹ: 10 Bi iwọ ba gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti a kọ sinu iwé ofin yi; bi iwọ ba si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ. 11 Nitori aṣẹ yi ti mo pa fun ọ li oni, kò ṣoro jù fun ọ, bẹ̃ni kò jìna rere si ọ. 12 Kò sí li ọrun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio gòke lọ si ọrun fun wa, ti yio si mú u wá fun wa, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? 13 Bẹ̃ni kò sí ni ìha keji okun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio rekọja okun lọ fun wa, ti yio si mú u fun wa wá, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? 14 Ṣugbọn ọ̀rọ na li o wà nitosi rẹ girigiri yi, li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ, ki iwọ ki o le ma ṣe e. 15 Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni; 16 Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. 17 Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn; 18 Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a. 19 Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ: 20 Ki iwọ ki o le ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki o le ma faramọ́ ọ: nitoripe on ni ìye rẹ, ati gigùn ọjọ́ rẹ: ki iwọ ki o le ma gbé inu ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, ati fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn.

Deuteronomi 31

Joṣua Gba Ipò Mose

1 MOSE si lọ, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli. 2 O si wi fun wọn pe, Emi di ẹni ọgọfa ọdún li oni; emi kò le ma jade ki nsi ma wọle mọ́: OLUWA si ti wi fun mi pe, Iwọ ki yio gòke Jordani yi mọ́. 3 OLUWA Ọlọrun rẹ, on ni yio rekọja ṣaju rẹ, on ni yio si run orilẹ-ède wọnyi kuro niwaju rẹ, iwọ o si gbà wọn: ati Joṣua, on ni yio gòke ṣaju rẹ, bi OLUWA ti wi. 4 OLUWA yio si ṣe si wọn bi o ti ṣe si Sihoni ati si Ogu, ọba awọn Amori, ati si ilẹ wọn; awọn ẹniti o run. 5 OLUWA yio si fi wọn tọrẹ niwaju nyin, ki ẹnyin ki o le fi wọn ṣe gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ ti mo pa fun nyin. 6 Ẹ ṣe giri ki ẹ si mu àiya le, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ, on li o mbá ọ lọ; on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ. 7 Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a. 8 Ati OLUWA on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ: máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ.

Kíka Òfin ní Ọdún Keje-keje

9 Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli. 10 Mose si paṣẹ fun wọn, wipe, Li opin ọdún meje meje li akokò ọdún idasilẹ, ni ajọ agọ́. 11 Nigbati gbogbo Israeli ba wá farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti on o gbé yàn, ki iwọ ki o kà ofin yi niwaju gbogbo Israeli li etí wọn. 12 Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi; 13 Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.

Ìlànà Ìkẹyìn Tí OLUWA fún Mose

14 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ́ rẹ sunmọ-etile ti iwọ o kú: pè Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ́ ajọ, ki emi ki o le fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ́ ajọ. 15 OLUWA si yọ si wọn ninu agọ́ na ninu ọwọ̀n awọsanma: ọwọ̀n awọsanma na si duro loke ẹnu-ọ̀na agọ́ na. 16 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá. 17 Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa? 18 Emi o fi oju mi pamọ́ patapata li ọjọ́ na, nitori gbogbo ìwabuburu ti nwọn o ti hù, nitori nwọn yipada si oriṣa. 19 Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ́ awọn ọmọ Israeli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ́ ẹrí fun mi si awọn ọmọ Israeli. 20 Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi. 21 Yio si ṣe, nigbati ibi pupọ̀ ati iyọnu ba bá wọn, ki orin yi ki o jẹri tì wọn bi ẹlẹri; nitoripe a ki yio gbagbé rẹ̀ lati ẹnu awọn ọmọ wọn: nitori mo mọ̀ ìro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mú wọn wá sinu ilẹ na ti mo bura si. 22 Nitorina ni Mose ṣe kọwe orin yi li ọjọ́ na gan, o si fi kọ́ awọn ọmọ Israeli. 23 O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ. 24 O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọ̀rọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari, 25 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nrù apoti majẹmu OLUWA, wipe, 26 Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o ma wà nibẹ̀ fun ẹrí si ọ. 27 Nitoripe mo mọ̀ ọ̀tẹ rẹ, ati lile ọrùn rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lãye sibẹ̀ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ̀ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA; melomelo si ni lẹhin ikú mi? 28 Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn. 29 Nitori mo mọ̀ pe lẹhin ikú mi ẹnyin o bà ara nyin jẹ́ patapata, ati pe ẹnyin o yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin; ibi yio si bá nyin li ọjọ́ ikẹhin; nitoriti ẹnyin o ma ṣe buburu li oju OLUWA, lati fi iṣẹ ọwọ́ nyin mu u binu.

Orin Mose

30 Mose si sọ ọ̀rọ orin yi li etí gbogbo ijọ Israeli, titi nwọn fi pari.

Deuteronomi 32

1 FETISILẸ, ẹnyin ọrun, emi o si sọ̀rọ; si gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi, iwọ aiye: 2 Ẹkọ́ mi yio ma kán bi ojò ohùn mi yio ma sẹ̀ bi ìri; bi òjo winiwini sara eweko titun, ati bi ọ̀wara òjo sara ewebẹ̀: 3 Nitoriti emi o kokikí orukọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fun Ọlọrun wa. 4 Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on. 5 Nwọn ti bà ara wọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, nwọn ki iṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni; iran arekereke ati wiwọ́ ni nwọn. 6 Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ́ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsẹ̀ rẹ mulẹ? 7 Ranti ọjọ́ igbãni, ronu ọdún iraniran: bi baba rẹ lere yio si fihàn ọ; bi awọn àgba rẹ, nwọn o si sọ fun ọ. 8 Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli. 9 Nitoripe ipín ti OLUWA li awọn enia rẹ̀; Jakobu ni ipín iní rẹ̀. 10 O ri i ni ilẹ aṣalẹ̀, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ̀, o pa a mọ́ bi ẹyin oju rẹ̀: 11 Bi idì ti irú itẹ́ rẹ̀, ti iràbaba sori ọmọ rẹ̀, ti inà iyẹ́-apa rẹ̀, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ́-apa rẹ̀: 12 Bẹ̃ni OLUWA nikan ṣamọ̀na rẹ̀, kò si sí oriṣa pẹlu rẹ̀. 13 O mu u gùn ibi giga aiye, ki o le ma jẹ eso oko; o si jẹ ki o mu oyin lati inu apata wá, ati oróro lati inu okuta akọ wá; 14 Ori-amọ́ malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹ̀jẹ eso-àjara, ani ọti-waini. 15 Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa: iwọ sanra tán, iwọ kì tan, ọrá bò ọ tán: nigbana li o kọ̀ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata ìgbala rẹ̀. 16 Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni nwọn fi mu u binu. 17 Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, si oriṣa ti o hù ni titun, ti awọn baba nyin kò bẹ̀ru. 18 Apata ti o bi ọ ni iwọ kò ranti, iwọ si ti gbagbé Ọlọrun ti o dá ọ. 19 OLUWA si ri i, o si korira wọn, nitori ìwa-imunibinu awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ̀. 20 O si wipe, Emi o pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, emi o si ma wò bi igbẹhin wọn yio ti ri; nitori iran alagídi ni nwọn, awọn ọmọ ninu ẹniti kò sí igbagbọ. 21 Nwọn ti fi ohun ti ki iṣe Ọlọrun mu mi jowú; nwọn si fi ohun asan wọn mu mi binu: emi o si fi awọn ti ki iṣe enia mu wọn jowú; emi o si fi aṣiwere orilẹ-ède mu wọn binu. 22 Nitoripe iná kan ràn ninu ibinu mi, yio si jó dé ipò-okú ni isalẹ, yio si run aiye pẹlu asunkún rẹ̀, yio si tinabọ ipilẹ awọn okenla. 23 Emi o kó ohun buburu jọ lé wọn lori; emi o si lò ọfà mi tán si wọn lara: 24 Ebi yio mu wọn gbẹ, oru gbigbona li a o fi run wọn, ati iparun kikorò; emi o si rán ehín ẹranko si wọn, pẹlu oró ohun ti nrakò ninu erupẹ. 25 Idà li ode, ati ipàiya ninu iyẹwu, ni yio run ati ọmọkunrin ati wundia, ọmọ ẹnu-ọmu, ati ọkunrin arugbo elewu irun pẹlu. 26 Mo wipe, Emi o tu wọn ká patapata, emi o si mu iranti wọn dá kuro ninu awọn enia: 27 Bikoṣepe bi mo ti bẹ̀ru ibinu ọtá, ki awọn ọtá wọn ki o má ba ṣe alaimọ̀, ati ki nwọn ki o má ba wipe, Ọwọ́ wa leke ni, ki isi ṣe OLUWA li o ṣe gbogbo eyi. 28 Nitori orilẹ-ède ti kò ní ìmọ ni nwọn, bẹ̃ni kò sí òye ninu wọn. 29 Ibaṣepe nwọn gbọ́n, ki òye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn! 30 Ẹnikan iba ti ṣe lé ẹgbẹrun, ti ẹni meji iba si lé ẹgbãrun sá, bikoṣepe bi Apata wọn ti tà wọn, ti OLUWA si fi wọn tọrẹ? 31 Nitoripe apata wọn kò dabi Apata wa, ani awọn ọtá wa tikalawọn ni nṣe onidajọ. 32 Nitoripe igi-àjara wọn, ti igi-àjara Sodomu ni, ati ti igbẹ́ Gomorra: eso-àjara wọn li eso-àjara orõro, ìdi wọn korò: 33 Ọti-waini wọn iwọ ti dragoni ni, ati oró mimu ti pamọlẹ̀. 34 Eyi ki a tojọ sọdọ mi ni ile iṣura, ti a si fi èdidi dì ninu iṣura mi? 35 Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsẹ̀ wọn yio yọ́: nitoriti ọjọ́ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ̀ wa bá wọn nyára wá. 36 Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù. 37 On o si wipe, Nibo li oriṣa wọn gbé wà, apata ti nwọn gbẹkẹle: 38 Ti o ti jẹ ọrá ẹbọ wọn, ti o ti mu ọti-waini ẹbọ ohunmimu wọn? jẹ ki nwọn dide ki nwọn si ràn nyin lọwọ, ki nwọn ṣe àbo nyin. 39 Wò o nisisiyi pe Emi, ani Emi ni, kò si sí ọlọrun pẹlu mi: mo pa, mo si sọ di ãye; mo ṣalọgbẹ, mo si mu jiná; kò si sí ẹnikan ti o le gbà silẹ li ọwọ́ mi. 40 Nitoripe mo gbé ọwọ́ mi soke ọrun, mo si wipe, Bi Emi ti wà titilai. 41 Bi mo ba si pọ́n idà didan mi, ti mo ba si fi ọwọ́ mi lé idajọ; emi o san ẹsan fun awọn ọtá mi, emi o radi i fun awọn ti o korira mi. 42 Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá. 43 Ẹ ma yọ̀, ẹnyin orilẹ-ède, pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on o gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀, yio si gbẹsan lara awọn ọtá rẹ̀, yio si ṣètutu fun ilẹ rẹ̀, ati fun awọn enia rẹ̀. 44 Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi li etí awọn enia na, on, ati Hoṣea ọmọ Nuni.

Ìlànà Ìkẹyìn tí Mose fún Wọn

45 Mose si pari sisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli: 46 O si wi fun wọn pe, Ẹ gbé ọkàn nyin lé gbogbo ọ̀rọ ti mo sọ lãrin nyin li oni; ti ẹnyin o palaṣẹ fun awọn ọmọ nyin lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi. 47 Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni, ati nipa eyi li ẹnyin o mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a. 48 OLUWA si sọ fun Mose li ọjọ́ na gan, wipe, 49 Gùn òke Abarimu yi lọ, si òke Nebo, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Jeriko; ki o si wò ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli ni iní. 50 Ki o si kú lori òke na, nibiti iwọ ngùn lọ, ki a si kó ọ jọ sọdọ awọn enia rẹ; bi Aaroni arakunrin rẹ ti kú li òke Horu, ti a si kó o jọ sọdọ awọn enia rẹ̀: 51 Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli. 52 Ṣugbọn iwọ o ri ilẹ na niwaju rẹ; ṣugbọn iwọ ki yio lọ sibẹ̀, si ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.

Deuteronomi 33

Mose Súre fún Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

1 EYI si ni ire, ti Mose enia Ọlọrun su fun awọn ọmọ Israeli ki o to kú. 2 O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá. 3 Nitõtọ, o fẹ́ awọn enia na; gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀ wà li ọwọ́ rẹ. Nwọn si joko li ẹsẹ̀ rẹ; olukuluku ni yio gbà ninu ọ̀rọ rẹ. 4 Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu. 5 O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀. 6 Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn. 7 Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀. 8 Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba; 9 Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́. 10 Nwọn o ma kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli li ofin rẹ: nwọn o ma mú turari wá siwaju rẹ, ati ọ̀tọtọ ẹbọ sisun sori pẹpẹ rẹ. 11 OLUWA, busi ohun-iní rẹ̀, ki o si tẹwọgbà iṣẹ ọwọ́ rẹ̀: lù ẹgbẹ́ awọn ti o dide si i, ati ti awọn ti o korira rẹ̀, ki nwọn ki o máṣe dide mọ́. 12 Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀. 13 Ati niti Josefu o wipe, Ibukún OLUWA ni ilẹ rẹ̀, fun ohun iyebiye ọrun, fun ìri, ati fun ibú ti o ba nisalẹ, 14 Ati fun eso iyebiye ti õrùn múwa, ati fun ohun iyebiye ti ndàgba li oṣoṣù, 15 Ati fun ohun pàtaki okenla igbãni, ati fun ohun iyebiye òke aiyeraiye, 16 Ati fun ohun iyebiye aiye ati ẹkún rẹ̀, ati fun ifẹ́ inurere ẹniti o gbé inu igbẹ́: jẹ ki ibukún ki o wá si ori Josefu, ati si atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. 17 Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse. 18 Ati niti Sebuluni o wipe, Sebuluni, ma yọ̀ ni ijade rẹ; ati Issakari, ninu agọ́ rẹ. 19 Nwọn o pè awọn enia na sori òke; nibẹ̀ ni nwọn o ru ẹbọ ododo: nitoripe nwọn o ma mu ninu ọ̀pọlọpọ okun, ati ninu iṣura ti a pamọ́ ninu iyanrin. 20 Ati niti Gadi o wipe, Ibukún ni fun ẹniti o mu Gadi gbilẹ: o ba bi abo-kiniun, o si fà apa ya, ani atari. 21 O si yàn apá ikini fun ara rẹ̀, nitoripe nibẹ̀ li a fi ipín olofin pamọ́ si; o si wá pẹlu awọn olori enia na, o si mú ododo OLUWA ṣẹ, ati idajọ rẹ̀ pẹlu Israeli. 22 Ati niti Dani o wipe, Ọmọ kiniun ni Dani: ti nfò lati Baṣani wá. 23 Ati niti Naftali o wipe, Iwọ Naftali, ti ojurere tẹ́lọrùn, ti o si kún fun ibukún OLUWA: gbà ìha ìwọ-õrùn ati gusù. 24 Ati niti Aṣeri o wipe, Ibukún ọmọ niti Aṣeri; ki on ki o si jẹ́ itẹwọgba fun awọn arakunrin rẹ̀, ki on ki o si ma rì ẹsẹ̀ rẹ̀ sinu oróro. 25 Bàta rẹ yio jasi irin ati idẹ; ati bi ọjọ́ rẹ, bẹ̃li agbara rẹ yio ri. 26 Kò sí ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ̀ li oju-ọrun. 27 Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà: on si tì ọtá kuro niwaju rẹ, o si wipe, Ma parun. 28 Israeli si joko li alafia, orisun Jakobu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti-waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ̀ nsẹ̀ ìri silẹ. 29 Alafia ni fun iwọ, Israeli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ́ OLUWA gbàla, asà iranlọwọ rẹ, ati ẹniti iṣe idà ọlanla rẹ! awọn ọtá rẹ yio si tẹriba fun ọ; iwọ o si ma tẹ̀ ibi giga wọn mọlẹ.

Deuteronomi 34

Ikú Mose

1 MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a; 2 Ati gbogbo Naftali, ati ilẹ Efraimu, ati ti Manasse, ati gbogbo ilẹ Juda, dé okun ìwọ-õrùn; 3 Ati gusù, ati pẹtẹlẹ̀ afonifoji Jeriko, ilu ọlọpẹ dé Soari. 4 OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀. 5 Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA. 6 O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni. 7 Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku. 8 Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari. 9 Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 10 Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju, 11 Ni gbogbo iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, ti OLUWA rán a lati ṣe ni ilẹ Egipti, si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀; 12 Ati ni gbogbo ọwọ́ agbara, ati ni gbogbo ẹ̀ru nla ti Mose fihàn li oju gbogbo Israeli.

Joṣua 1

Ọlọrun Pàṣẹ fún Joṣua pé Kí Ó Fi Ogun Kó Ilẹ̀ Kenaani

1 O si ṣe lẹhin ikú Mose iranṣẹ OLUWA, li OLUWA sọ fun Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, wipe, 2 Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli. 3 Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀, ẹnyin ni mo fi fun, gẹgẹ bi mo ti sọ fun Mose. 4 Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin. 5 Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. 6 Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn. 7 Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ. 8 Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ. 9 Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.

Joṣua Pàṣẹ fún Àwọn Eniyan Náà

10 Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe, 11 Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní. 12 Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe, 13 Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi. 14 Awọn obinrin nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, yio joko ni ilẹ ti Mose fi fun nyin ni ìha ihin Jordani; ṣugbọn ẹnyin o gòke lọ niwaju awọn arakunrin nyin ni ihamọra, gbogbo awọn alagbara akọni, ẹnyin o si ràn wọn lọwọ, 15 Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i. 16 Nwọn si da Joṣua lohùn, wipe, Gbogbo ohun ti iwọ palaṣẹ fun wa li awa o ṣe, ibikibi ti iwọ ba rán wa lọ, li awa o lọ. 17 Gẹgẹ bi awa ti gbọ́ ti Mose li ohun gbogbo, bẹ̃li awa o gbọ́ tirẹ: kìki ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o wà pẹlu rẹ, gẹgẹ bi o ti wà pẹlu Mose. 18 Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.

Joṣua 2

Joṣua Rán Àwọn Amí Lọ sí Jẹriko

1 JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀. 2 A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò. 3 Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò. 4 Obinrin na si mú awọn ọkunrin meji na, o si fi wọn pamọ́; o si wi bayi pe, Awọn ọkunrin kan wá sọdọ mi, ṣugbọn emi kò mọ̀ ibi ti nwọn ti wá. 5 O si ṣe li akokò ati tì ilẹkun ẹnubode, nigbati ilẹ ṣú, awọn ọkunrin na si jade lọ: ibi ti awọn ọkunrin na gbé lọ, emi kò mọ̀: ẹ lepa wọn kánkán; nitori ẹnyin o bá wọn. 6 Ṣugbọn o ti mú wọn gòke àja ile, o si fi poroporo ọ̀gbọ ti o ti tòjọ soke àja bò wọn mọlẹ. 7 Awọn ọkunrin na lepa wọn li ọ̀na ti o lọ dé iwọ̀do Jordani: bi awọn ti nlepa wọn si ti jade lọ, nwọn tì ilẹkun ẹnubode. 8 Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja; 9 O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin. 10 Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu. 11 Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye. 12 Njẹ nitorina, emi bẹ̀ nyin, ẹ fi OLUWA bura fun mi, bi mo ti ṣe nyin li ore, ẹnyin o ṣe ore pẹlu fun ile baba mi, ẹnyin o si fun mi li àmi otitọ: 13 Ati pe ẹnyin o pa baba mi mọ́ lãye, ati iya mi, ati awọn arakunrin mi, ati awọn arabinrin mi, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, ki ẹnyin si gbà ẹmi wa lọwọ ikú. 14 Awọn ọkunrin na da a lohùn pe, Ẹmi wa ni yio dipò ti nyin, bi ẹnyin kò ba fi ọ̀ran wa yi hàn; yio si ṣe, nigbati OLUWA ba fun wa ni ilẹ na, awa o ṣe ore ati otitọ fun ọ. 15 Nigbana li o fi okùn sọ̀ wọn kalẹ li oju-ferese: nitoriti ile rẹ̀ wà lara odi ilu, on a si ma gbé ori odi na. 16 O si wi fun wọn pe, Ẹ bọ sori òke, ki awọn alepa ki o má ba le nyin bá; ki ẹnyin si fara nyin pamọ́ nibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa yio fi pada: lẹhin na ẹ ma ba ọ̀na ti nyin lọ. 17 Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú. 18 Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ. 19 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a. 20 Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi. 21 O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese. 22 Nwọn si lọ, nwọn si dé ori òke, nwọn si gbé ibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa fi pada: awọn alepa wá wọn ni gbogbo ọ̀na, ṣugbọn nwọn kò ri wọn. 23 Bẹ̃li awọn ọkunrin meji na pada, nwọn si sọkalẹ lori òke, nwọn si kọja, nwọn si tọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wá; nwọn si sọ ohun gbogbo ti o bá wọn fun u. 24 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.

Joṣua 3

Àwọn Ọmọ Israẹli La Odò Jọdani Kọjá

1 JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò. 2 O si ṣe lẹhin ijọ́ mẹta, ni awọn olori là ãrin ibudó já; 3 Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin. 4 Ṣugbọn alafo yio wà li agbedemeji ti ẹnyin tirẹ̀, to bi ìwọn ẹgba igbọnwọ: ẹ má ṣe sunmọ ọ, ki ẹnyin ki o le mọ̀ ọ̀na ti ẹnyin o gbà; nitoriti ẹnyin kò gbà ọ̀na yi rí. 5 Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin. 6 Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia. 7 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ. 8 Iwọ o si paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na pe, Nigbati ẹnyin ba dé eti odò Jordani, ki ẹnyin ki o duro jẹ ni Jordani. 9 Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ ihin, ki ẹ si gbọ́ ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun nyin. 10 Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin. 11 Kiyesi i, apoti majẹmu OLUWA gbogbo aiye ngòke lọ ṣaju nyin lọ si Jordani. 12 Njẹ nitorina, ẹ mu ọkunrin mejila ninu awọn ẹ̀ya Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya. 13 Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan. 14 O si ṣe, nigbati awọn enia ṣí kuro ninu agọ́ wọn, lati gòke Jordani, ti awọn alufa si rù apoti majẹmu wà niwaju awọn enia; 15 Bi awọn ti o rù apoti si ti dé Jordani, ti awọn alufa ti o rù apoti na si tẹ̀ ẹsẹ̀ wọn bọ̀ eti omi na, (nitoripe odò Jordani a ma kún bò gbogbo bèbe rẹ̀ ni gbogbo akokò ikore,) 16 Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko. 17 Awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jordani, ati gbogbo awọn enia Israeli kọja lori ilẹ gbigbẹ, titi gbogbo awọn enia na fi gòke Jordani tán.

Joṣua 4

Wọ́n To Òkúta Ìrántí Jọ

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia rekọja Jordani tán, ni OLUWA wi fun Joṣua pe, 2 Mú ọkunrin mejila ninu awọn enia, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya, 3 Ki ẹnyin si paṣẹ fun wọn pe. Ẹ gbé okuta mejila lati ihin lọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa gbé duro ṣinṣin nì, ki ẹnyin ki o si rù wọn kọja pẹlu nyin, ẹ si fi wọn si ibùsun, ni ibi ti ẹnyin o sùn li alẹ yi. 4 Nigbana ni Joṣua pè awọn ọkunrin mejila, ti o ti pèse silẹ ninu awọn ọmọ Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya: 5 Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ kọja lọ niwaju apoti OLUWA Ọlọrun nyin si ãrin Jordani, ki olukuluku ninu nyin ki o gbé okuta kọkan lé ejika rẹ̀, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli: 6 Ki eyi ki o le jẹ́ àmi lãrin nyin, nigbati awọn ọmọ nyin ba bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la, wipe, Èredi okuta wọnyi? 7 Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai. 8 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi Joṣua ti paṣẹ, nwọn si gbé okuta mejila lati inu ãrin Jordani lọ, bi OLUWA ti wi fun Joṣua, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; nwọn si rù wọn kọja pẹlu wọn lọ si ibùsun, nwọn si gbé wọn kalẹ nibẹ̀. 9 Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni. 10 Nitoriti awọn alufa ti o rù apoti na duro lãrin Jordani, titi ohun gbogbo fi pari ti OLUWA palaṣẹ fun Joṣua lati sọ fun awọn enia, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Mose palaṣẹ fun Joṣua: awọn enia na si yára nwọn si rekọja. 11 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia. 12 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn: 13 Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko. 14 Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo. 15 OLUWA si wi fun Joṣua pe, 16 Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade. 17 Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade. 18 O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju. 19 Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko. 20 Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali. 21 O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi? 22 Nigbana li ẹnyin o jẹ ki awọn ọmọ nyin ki o mọ̀ pe, Israeli là Jordani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ. 23 Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja: 24 Ki gbogbo enia aiye ki o le mọ ọwọ́ OLUWA, pe o lagbara; ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin lailai.

Joṣua 5

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli. 2 Nigbana li OLUWA wi fun Joṣua pe, Fi okuta ṣe abẹ ki iwọ ki o si tun kọ awọn ọmọ Israeli nilà lẹ̃keji. 3 Joṣua si ṣe abẹ okuta, o si kọ awọn ọmọ Israeli nilà, ni Gibeati-haaralotu. 4 Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti. 5 Nitori gbogbo awọn enia ti o jade ti ibẹ̀ wà, a kọ wọn nilà: ṣugbọn gbogbo awọn enia ti a bi li aginjù li ọ̀na, bi nwọn ti jade kuro ni Egipti, awọn ni a kò kọnilà. 6 Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn li ogoji ọdún li aginjù, titi gbogbo iran na, ani awọn ologun, ti o jade ti Egipti wá fi run, nitoriti nwọn kò gbà ohùn OLUWA gbọ́: awọn ti OLUWA bura fun pe, on ki yio jẹ ki wọn ri ilẹ na, ti OLUWA bura fun awọn baba wọn lati fi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. 7 Ati awọn ọmọ wọn, ti o gbé dide ni ipò wọn, awọn ni Joṣua kọnilà: nitoriti nwọn wà li alaikọlà, nitoriti a kò kọ wọn nilà li ọ̀na. 8 O si ṣe, nigbati nwọn kọ gbogbo awọn enia na nilà tán, nwọn joko ni ipò wọn ni ibudó, titi ara wọn fi dá. 9 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni ni mo yi ẹ̀gan Egipti kuro lori nyin. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ ni Gilgali titi o fi di oni yi. 10 Awọn ọmọ Israeli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla oṣù li ọjọ́ alẹ, ni pẹtẹlẹ̀ Jeriko. 11 Nwọn si jẹ ọkà gbigbẹ ilẹ na ni ijọ́ keji lẹhin irekọja, àkara alaiwu, ọkà didin li ọjọ̀ na gan. 12 Manna si dá ni ijọ́ keji lẹhin igbati nwọn ti jẹ okà gbigbẹ ilẹ na; awọn ọmọ Israeli kò si ri manna mọ́; ṣugbọn nwọn jẹ eso ilẹ Kenaani li ọdún na.

Joṣua ati Ẹni Tí Ó Mú Idà Lọ́wọ́

13 O si ṣe, nigbati Joṣua wà leti Jeriko, o gbé oju rẹ̀ soke o si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan duro niwaju rẹ̀ pẹlu idà fifayọ li ọwọ́ rẹ̀: Joṣua si tọ̀ ọ lọ, o si wi fun u pe, Ti wa ni iwọ nṣe, tabi ti ọtá wa? 14 O si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi. Joṣua si wolẹ niwaju rẹ̀, o si foribalẹ, o si wi fun pe, Kili oluwa mi ni isọ fun iranṣẹ rẹ̀? 15 Olori-ogun OLUWA si wi fun Joṣua pe, Bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ; nitoripe ibi ti iwọ gbé duro nì ibi mimọ́ ni. Joṣua si ṣe bẹ̃.

Joṣua 6

Wíwó Odi Jẹriko

1 (NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.) 2 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni. 3 Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa. 4 Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni. 5 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba fọn ipè jubeli kikan, nigbati ẹnyin ba si gbọ́ iró ipè na, gbogbo awọn enia yio si hó kũ; odi ilu na yio si wó lulẹ, bẹrẹ, awọn enia yio si gòke lọ tàra, olukuluku niwaju rẹ̀. 6 Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA. 7 O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA. 8 O si ṣe, nigbati Joṣua wi fun awọn enia tán, awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje, kọja niwaju OLUWA nwọn si fọn ipè wọnni: apoti majẹmu OLUWA si tẹle wọn. 9 Awọn ti o hamọra si lọ niwaju awọn alufa, ti nfọn ipè, ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti lẹhin, awọn alufa nlọ nwọn si nfọn ipè. 10 Joṣua si paṣẹ fun awọn enia wipe, Ẹ kò gbọdọ hó bẹ̃li ẹ kò gbọdọ pariwo, bẹ̃li ọ̀rọ kan kò gbọdọ jade li ẹnu nyin, titi ọjọ́ ti emi o wi fun nyin pe, ẹ hó; nigbana li ẹnyin o hó. 11 Bẹ̃li o mu ki apoti OLUWA ki o yi ilu na ká, o yi i ká lẹ̃kan: nwọn si lọ si ibudó, nwọn si wọ̀ ni ibudó. 12 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA. 13 Awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje niwaju apoti OLUWA nlọ titi, nwọn si nfọn ipè wọnni: awọn ti o hamọra-ogun nlọ niwaju wọn; ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti OLUWA lẹhin, awọn alufa si nfọn ipè bi nwọn ti nlọ. 14 Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa. 15 O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje. 16 O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na. 17 Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́. 18 Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a. 19 Ṣugbọn gbogbo fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati ti irin, mimọ́ ni fun OLUWA: nwọn o wá sinu iṣura OLUWA. 20 Bẹ̃li awọn enia na hó, nigbati awọn alufa fọn ipè: o si ṣe, nigbati awọn enia gbọ́ iró ipè, ti awọn enia si hó kũ, odi na wólulẹ bẹrẹ, bẹ̃li awọn enia wọ̀ inu ilu na lọ, olukuluku tàra niwaju rẹ̀, nwọn si kó ilu na. 21 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ohun ti o wà ni ilu na run, ati ọkunrin ati obinrin, ati ewe ati àgba, ati akọ-mãlu, ati agutan, ati kẹtẹkẹtẹ. 22 Ṣugbọn Joṣua sọ fun awọn ọkunrin meji ti o ti ṣe amí ilẹ na pe, Ẹ lọ si ile panṣaga nì, ki ẹ si mú obinrin na jade nibẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, gẹgẹ bi ẹnyin ti bura fun u. 23 Awọn ọmọkunrin ti o ṣamí si wọle, nwọn si mú Rahabu jade, ati baba rẹ̀, ati iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, nwọn si mú gbogbo awọn ibatan rẹ̀ jade; nwọn si fi wọn si ẹhin ibudó Israeli. 24 Nwọn si fi iná kun ilu na ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀; kìki fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati irin, ni nwọn fi sinu iṣura ile OLUWA. 25 Joṣua si gbà Rahabu panṣaga là, ati ara ile baba rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; o si joko lãrin Israeli titi di oni-oloni; nitoriti o pa awọn onṣẹ mọ́ ti Joṣua rán lọ ṣamí Jeriko. 26 Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró. 27 Bẹ̃ni OLUWA wà pẹlu Joṣua; okikí rẹ̀ si kàn ká gbogbo ilẹ na.

Joṣua 7

Ẹ̀ṣẹ̀ Akani

1 ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli. 2 Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai. 3 Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn. 4 Bẹ̃ni ìwọn ẹgbẹdogun enia gòke lọ sibẹ̀: nwọn si sá niwaju awọn enia Ai. 5 Awọn enia Ai pa enia mẹrindilogoji ninu wọn: nwọn si lepa wọn lati ẹnubode titi dé Ṣebarimu, nwọn si pa wọn bi nwọn ti nsọkalẹ: àiya awọn enia na já, o si di omi. 6 Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn. 7 Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani! 8 A, Oluwa, kili emi o wi, nigbati Israeli pa ẹhin wọn dà niwaju awọn ọtá wọn! 9 Nitoriti awọn ara Kenaani ati gbogbo awọn ara ilẹ na yio gbọ́, nwọn o si yi wa ká, nwọn o si ke orukọ wa kuro li aiye: kini iwọ o ha ṣe fun orukọ nla rẹ? 10 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi? 11 Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn. 12 Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin. 13 Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin. 14 Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan. 15 Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli. 16 Bẹ̃ni Joṣua dide ni kùtukutu owurọ̀, o si mú Israeli wá gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; a si mú ẹ̀ya Juda: 17 O si mú idile Juda wá; a si mu idile Sera: o si mú idile Sera wá li ọkunrin kọkan; a si mú Sabdi: 18 O si mú ara ile rẹ̀ li ọkunrin kọkan; a si mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ninu, ẹ̀ya Judah. 19 Joṣua si wi fun Akani pe, Ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, fi ogo fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, ki o si jẹwọ fun u; ki o si sọ fun mi nisisiyi, ohun ti iwọ se; má ṣe pa a mọ́ fun mi. 20 Akani si da Joṣua lohùn, o si wipe, Nitõtọ ni mo ṣẹ̀ si OLUWA, Ọlọrun Israeli, bayi bayi ni mo ṣe: 21 Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀. 22 Joṣua si rán onṣẹ, nwọn si sare wọ̀ inu agọ́ na; si kiyesi i, a fi i pamọ́ ninu agọ́ rẹ̀, ati fadakà labẹ rẹ̀. 23 Nwọn si mú wọn jade lãrin agọ́ na, nwọn si mú wọn wá sọdọ Joṣua, ati sọdọ gbogbo awọn ọmọ Israeli, nwọn si fi wọn lelẹ niwaju OLUWA. 24 Joṣua, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si mú Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹ̀wu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ati akọ-mãlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati agutan rẹ̀, ati agọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; nwọn si mú wọn lọ si ibi afonifoji Akoru. 25 Joṣua si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yọ wa lẹnu? OLUWA yio yọ iwọ na lẹnu li oni yi. Gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta. 26 Nwọn si kó òkiti okuta nla kan lé e lori titi di oni-oloni; OLUWA si yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ li Afonifoji Akoru, titi di oni-oloni.

Joṣua 8

Gbígbà ati Pípa Ìlú Ai Run

1 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai, ati awọn enia rẹ̀, ati ilunla rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀ lé ọ lọwọ: 2 Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na. 3 Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru. 4 O si paṣẹ fun wọn pe, Wò o, ẹnyin o ba tì ilu na, ani lẹhin ilu na: ẹ má ṣe jìna pupọ̀ si ilu na, ṣugbọn ki gbogbo nyin ki o murasilẹ. 5 Ati emi, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu mi, yio sunmọ ilu na: yio si ṣe, nigbati nwọn ba jade si wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju, awa o si sá niwaju wọn; 6 Nitoriti nwọn o jade si wa, titi awa o fi fà wọn jade kuro ni ilu; nitoriti nwọn o wipe, Nwọn sá niwaju wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju; nitorina li awa o sá niwaju wọn: 7 Nigbana li ẹnyin o dide ni buba, ẹnyin o si gbà ilu na: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin yio fi i lé nyin lọwọ. 8 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gbà ilu na tán, ki ẹnyin ki o si tinabọ ilu na; gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA ni ki ẹnyin ki o ṣe: wò o, mo ti fi aṣẹ fun nyin na. 9 Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia. 10 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si kà awọn enia, o si gòke lọ si Ai, on, ati awọn àgba Israeli niwaju awọn enia. 11 Ati gbogbo awọn enia, ani awọn ọmọ-ogun ti mbẹ pẹlu rẹ̀, nwọn gòke lọ, nwọn si sunmọtosi, nwọn si wá siwaju ilu na, nwọn si dó ni ìha ariwa Ai; afonifoji si mbẹ li agbedemeji wọn ati Ai. 12 O si mú to bi ẹgbẹdọgbọ̀n enia, o si fi wọn si ibuba li agbedemeji Betieli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn ilu na. 13 Nwọn si yàn awọn enia si ipò, ani gbogbo ogun ti mbẹ ni ìha ariwa ilu na, ati awọn enia ti o ba ni ìha ìwọ-õrùn ilu na; Joṣua si lọ li oru na sãrin afonifoji na. 14 O si ṣe, nigbati ọba Ai ri i, nwọn yára nwọn si dide ni kùtukutu, awọn ọkunrin ilu na si jade si Israeli lati jagun, ati on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, niwaju pẹtẹlẹ̀, ibi ti a ti yàn tẹlẹ; ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn ti o ba dè e mbẹ lẹhin ilu. 15 Joṣua ati gbogbo awọn Israeli si ṣe bi ẹniti a lé niwaju wọn, nwọn si sá gbà ọ̀na aginjú. 16 A si pe gbogbo enia ti mbẹ ni Ai jọ lati lepa wọn: nwọn si lepa Joṣua, a si fà wọn jade kuro ni ilu. 17 Kò si kù ọkunrin kan ni Ai tabi Beti-eli, ti kò jade tọ̀ Israeli: nwọn si fi ilú nla silẹ ni ṣíṣí nwọn si lepa Israeli. 18 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Nà ọ̀kọ ti mbẹ li ọwọ́ rẹ nì si Ai; nitoriti emi o fi i lé ọ lọwọ. Joṣua si nà ọ̀kọ na ti o ni li ọwọ́ rẹ̀ si ilu na. 19 Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na. 20 Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa. 21 Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai. 22 Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn. 23 Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua. 24 O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u. 25 O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai. 26 Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu. 27 Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua. 28 Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni. 29 Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

Joṣua Ka Òfin ní Òkè Ebali

30 Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali, 31 Gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwé ofin Mose, pẹpẹ odidi okuta, lara eyiti ẹnikan kò fi irin kan: nwọn si ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA, nwọn si ru ẹbọ alafia. 32 O si kọ apẹrẹ ofin Mose sara okuta na, ti o kọ niwaju awọn ọmọ Israeli. 33 Ati gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori, ati awọn onidajọ wọn, duro li apa ihin ati li apa ọhún apoti ẹrí niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti o rù apoti majẹmu OLUWA, ati alejò ati ibilẹ; àbọ wọn kọjusi òke Gerisimu; ati àbọ wọn kọjusi òke Ebali, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ rí, pe ki nwọn ki o sure fun awọn enia Israeli. 34 Lẹhin eyi o si kà gbogbo ọ̀rọ ofin, ibukún ati egún, gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ ninu iwé ofin. 35 Kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo eyiti Mose palaṣẹ, ti Joṣua kò kà niwaju gbogbo ijọ Israeli, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹrẹ, ati awọn alejò ti nrìn lãrin wọn.

Joṣua 9

Àwọn Ará Gibeoni Tan Joṣua Jẹ

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ; 2 Nwọn si kó ara wọn jọ, lati fi ìmọ kan bá Joṣua ati Israeli jà. 3 Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai, 4 Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì; 5 Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi. 6 Nwọn si tọ̀ Joṣua lọ ni ibudó ni Gilgali, nwọn si wi fun u, ati fun awọn ọkunrin Israeli pe, Ilu òkere li awa ti wá; njẹ nitorina ẹ bá wa dá majẹmu. 7 Awọn ọkunrin Israeli si wi fun awọn Hifi pe, Bọya ẹnyin ngbé ãrin wa; awa o ti ṣe bá nyin dá majẹmu? 8 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Joṣua si wi fun wọn pe, Tali ẹnyin? nibo li ẹnyin si ti wá? 9 Nwọn si wi fun u pe, Ni ilu òkere rére li awọn iranṣẹ rẹ ti wá, nitori orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti awa ti gbọ́ okikí rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ṣe ni Egipti, 10 Ati ohun gbogbo ti o ṣe si awọn ọba awọn Amori meji, ti mbẹ ni òke Jordani, si Sihoni ọba Heṣboni, ati si Ogu ọba Baṣani, ti mbẹ ni Aṣtarotu. 11 Awọn àgba wa ati gbogbo awọn ara ilu wa sọ fun wa pe, Ẹ mú onjẹ li ọwọ́ nyin fun àjo na, ki ẹ si lọ ipade wọn, ki ẹ si wi fun wọn pe, Iranṣẹ nyin li awa iṣe: njẹ nitorina, ẹ bá wa dá majẹmu. 12 Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu: 13 Ìgo-awọ waini wọnyi, ti awa kún, titun ni nwọn; kiyesi i, nwọn fàya: ati ẹ̀wu wa wọnyi ati bàta wa di gbigbo nitori ọ̀na ti o jìn jù. 14 Awọn ọkunrin si gbà ninu onjẹ wọn, nwọn kò si bère li ẹnu OLUWA. 15 Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn. 16 O si ṣe li opin ijọ́ mẹta, lẹhin ìgbati nwọn bá wọn dá majẹmu, ni nwọn gbọ́ pe aladugbo wọn ni nwọn, ati pe làrin wọn ni nwọn gbé wà. 17 Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu. 18 Awọn ọmọ Israeli kò pa wọn, nitoriti awọn olori ijọ awọn enia ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn. Gbogbo ijọ awọn enia si kùn si awọn olori. 19 Ṣugbọn gbogbo awọn olori wi fun gbogbo ijọ pe, Awa ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn. 20 Eyi li awa o ṣe si wọn, ani awa o da wọn si, ki ibinu ki o má ba wà lori wa, nitori ibura ti a bura fun wọn. 21 Awọn olori si wi fun wọn pe, Ẹ da wọn si: nwọn si di aṣẹ́gi ati apọnmi fun gbogbo ijọ; gẹgẹ bi awọn olori ti sọ fun wọn. 22 Joṣua si pè wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi tàn wa wipe, Awa jìna rére si nyin; nigbati o jẹ́ pe lãrin wa li ẹnyin ngbé? 23 Njẹ nitorina ẹnyin di ẹni egún, ẹrú li ẹnyin o si ma jẹ́ titi, ati aṣẹ́gi ati apọnmi fun ile Ọlọrun mi. 24 Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi. 25 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, li ọwọ́ rẹ li awa wà: bi o ti dara si ati bi o ti tọ́ si li oju rẹ lati ṣe wa, ni ki iwọ ki o ṣe. 26 Bẹ̃li o si ṣe wọn, o si gbà wọn li ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si pa wọn. 27 Joṣua si ṣe wọn li aṣẹ́gi ati apọnmi fun ijọ, ati fun pẹpẹ OLUWA li ọjọ́ na, ani titi di oni-oloni, ni ibi ti o ba yàn.

Joṣua 10

Wọ́n Ṣẹgun Àwọn Ará Amori

1 O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn; 2 Nwọn bẹ̀ru pipọ̀, nitoriti Gibeoni ṣe ilu nla, bi ọkan ninu awọn ilu ọba, ati nitoriti o tobi jù Ai lọ, ati gbogbo ọkunrin inu rẹ̀ jẹ́ alagbara. 3 Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe, 4 Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ. 5 Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u. 6 Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa. 7 Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni. 8 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ. 9 Joṣua si yọ si wọn lojijì; o si gòke lati Gilgali lọ ni gbogbo oru na. 10 OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda. 11 O si ṣe, bi nwọn ti nsá niwaju Israeli, ti nwọn dé gẹrẹgẹrẹ Beti-horoni, OLUWA rọ̀ yinyin nla si wọn lati ọrun wá titi dé Aseka, nwọn si kú: awọn ti o ti ipa yinyin kú, o pọ̀ju awọn ti awọn ọmọ Israeli fi idà pa lọ. 12 Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni. 13 Õrùn si duro jẹ, oṣupa si duro, titi awọn enia fi gbẹsan lara awọn ọtá wọn. A kò ha kọ eyi nã sinu iwé Jaṣeri? Bẹ̃li õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ̀ nìwọn ọjọ́ kan tọ̀tọ. 14 Kò sí ọjọ́ ti o dabi rẹ̀ ṣaju rẹ̀ tabi lẹhin rẹ̀, ti OLUWA gbọ́ ohùn enia: nitoriti OLUWA jà fun Israeli. 15 Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.

Joṣua Fi Ogun Kó Àwọn Ọba Amori Maraarun

16 Ṣugbọn awọn ọba marun nì sá, nwọn si fara wọn pamọ́ ni ihò kan ni Makkeda. 17 A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda. 18 Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn: 19 Ṣugbọn ẹnyin, ẹ má ṣe duro, ẹ lepa awọn ọtá nyin, ki ẹ si kọlù wọn lẹhin; ẹ máṣe jẹ ki nwọn ki o wọ̀ ilu wọn lọ: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi wọn lé nyin lọwọ. 20 O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ, 21 Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli. 22 Nigbana ni Joṣua wipe, Ẹ ṣi ẹnu ihò na, ki ẹ si mú awọn ọba mararun na jade kuro ninu ihò tọ̀ mi wá. 23 Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni. 24 O si ṣe, nigbati nwọn mú awọn ọba na tọ̀ Joṣua wá, ni Joṣua pè gbogbo awọn ọkunrin Israeli, o si wi fun awọn olori awọn ọmọ-ogun ti o bá a lọ pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ si fi ẹsẹ̀ nyin lé ọrùn awọn ọba wọnyi. Nwọn si sunmọ wọn, nwọn si gbé ẹsẹ̀ wọn lé wọn li ọrùn. 25 Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà. 26 Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ. 27 O si ṣe li akokò ìwọ-õrùn, Joṣua paṣẹ, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ kuro lori igi, nwọn si gbé wọn sọ sinu ihò na ninu eyiti nwọn ti sapamọ́ si, nwọn si fi okuta nla di ẹnu ihò na, ti o wà titi di oni-oloni.

Joṣua Tún Gba Àwọn Ìlú Amori Mìíràn Sí i

28 Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko. 29 Joṣua si kọja lati Makkeda lọ si Libna, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si fi ijà fun Libna: 30 OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko. 31 Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u. 32 OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna. 33 Nigbana ni Horamu ọba Geseri gòke lati ràn Lakiṣi lọwọ; Joṣua si kọlù u ati awọn enia rẹ̀, tobẹ̃ ti kò fi kù ẹnikan silẹ fun u. 34 Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u; 35 Nwọn si kó o li ọjọ́ na, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ li o parun patapata li ọjọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Lakiṣi. 36 Joṣua si gòke lati Egloni lọ si Hebroni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si fi ijà fun u: 37 Nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù enikan silẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Egloni; o si pa a run patapata, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀. 38 Joṣua si pada lọ si Debiri, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; o si fi ijà fun u: 39 O si kó o, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀; nwọn si fi oju idà kọlù wọn; nwọn si pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ run patapata; kò si kù ẹnikan silẹ: gẹgẹ bi o ti ṣe si Hebroni, bẹ̃li o ṣe si Debiri, ati ọba rẹ̀; ati gẹgẹ bi o ti ṣe si Libna, ati ọba rẹ̀. 40 Bẹ̃ni Joṣua kọlù gbogbo ilẹ, ilẹ òke, ati ti Gusù, ati ti pẹtẹlẹ̀, ati ti ẹsẹ̀-òke, ati awọn ọba wọn gbogbo; kò kù ẹnikan silẹ: ṣugbọn o pa ohun gbogbo ti nmí run patapata, gẹgẹ bi OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti pa a laṣẹ. 41 Joṣua si kọlù wọn lati Kadeṣi-barnea lọ titi dé Gasa, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ani titi dé Gibeoni. 42 Ati gbogbo awọn ọba wọnyi ati ilẹ wọn, ni Joṣua kó ni ìgba kanna, nitoriti OLUWA, Ọlọrun Israeli, jà fun Israeli. 43 Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.

Joṣua 11

Joṣua Ṣẹgun Jabini ati Àwọn tí Wọ́n Darapọ̀ Mọ́ ọn

1 O si ṣe, nigbati Jabini ọba Hasoru gbọ́ nkan wọnyi, o ranṣẹ si Jobabu ọba Madoni, ati si ọba Ṣimroni, ati si ọba Akṣafu, 2 Ati si awọn ọba ti mbẹ ni ìha ariwa, lori òke, ati ti pẹtẹlẹ̀ ni ìha gusù ti Kinnerotu, ati ni ilẹ titẹju, ati ni ilẹ òke Doru ni ìha ìwọ-õrùn, 3 Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa. 4 Nwọn si jade, awọn ati gbogbo ogun wọn pẹlu wọn, ọ̀pọlọpọ enia, bi yanrin ti mbẹ li eti okun fun ọ̀pọ, ati ẹṣin ati kẹkẹ́ pipọ̀pipọ. 5 Gbogbo awọn ọba wọnyi si pejọ pọ̀, nwọn wá nwọn si dó ṣọkan ni ibi omi Meromu, lati fi ijà fun Israeli. 6 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn. 7 Bẹ̃ni Joṣua, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, yọ si wọn lojijì ni ibi omi Meromu, nwọn si kọlù wọn. 8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn. 9 Joṣua si ṣe si wọn gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o já patì ẹṣin wọn, o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn. 10 Joṣua si pada li akokò na, o si kó Hasoru, o si fi idà pa ọba rẹ̀: nitori li atijọ́ rí Hasoru li olori gbogbo ilẹ-ọba wọnni. 11 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, nwọn run wọn patapata: a kò kù ẹnikan ti nmí silẹ: o si fi iná kun Hasoru. 12 Ati gbogbo ilu awọn ọba wọnni, ati gbogbo ọba wọn, ni Joṣua kó, o si fi oju idà kọlù wọn, o si pa wọn run patapata, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti palaṣẹ. 13 Ṣugbọn awọn ilu ti o duro lori òke wọn, Israeli kò sun ọkan ninu wọn, bikoṣe Hasoru nikan; eyi ni Joṣua fi iná sun. 14 Ati gbogbo ikogun ilu wonyi, ati ohunọ̀sin, ni awọn ọmọ Israeli kó fun ara wọn; ṣugbọn gbogbo awọn ọkunrin ni nwọn fi oju kọlù, titi nwọn fi pa wọn run, nwọn kò kù ẹnikan silẹ ti nmí. 15 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, bẹ̃ni Mose paṣẹ fun Joṣua: bẹ̃ni Joṣua si ṣe; on kò kù ohun kan silẹ ninu gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ fun Mose.

Àwọn Ilẹ̀ Tí Joṣua Gbà

16 Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, ilẹ òke, ati gbogbo ilẹ Gusù, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ati ilẹ titẹju, ati pẹtẹlẹ̀, ati ilẹ òke Israeli, ati ilẹ titẹju rẹ̀; 17 Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn. 18 Joṣua si bá gbogbo awọn ọba wọnni jagun li ọjọ́ pipọ̀. 19 Kò sí ilu kan ti o bá awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ, bikoṣe awọn Hifi awọn ara ilu Gibeoni: gbogbo wọn ni nwọn fi ogun gbà. 20 Nitori lati ọdọ OLUWA li a ti mu ọkàn wọn le, ki nwọn ki o le jade ogun tọ̀ Israeli wá, ki o le pa wọn run patapata, ki nwọn ki o má si ṣe ri ojurere, ṣugbọn ki o le pa wọn run, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. 21 Li akokò na ni Joṣua wá, ti o si ke awọn ọmọ Anaki kuro ni ilẹ òke, kuro ni Hebroni, kuro ni Debiri, kuro ni Anabu, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Juda, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Israeli: Joṣua run wọn patapata pẹlu ilu wọn. 22 Kò kù ẹnikan ninu awọn ọmọ Anaki ni ilẹ awọn ọmọ Israeli: bikoṣe ni Gasa, ni Gati, ati ni Aṣdodu, ni nwọn kù si. 23 Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.

Joṣua 12

Àwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun

1 NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun: 2 Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni; 3 Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga: 4 Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei, 5 O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni. 6 Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun

7 Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn. 8 Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: 9 Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan. 10 Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan; 11 Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan; 12 Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan; 13 Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan; 14 Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan; 15 Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan; 16 Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan; 17 Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan; 18 Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan; 19 Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan; 20 Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan; 21 Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan; 22 Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan; 23 Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan; 24 Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n.

Joṣua 13

Ilẹ̀ Tí Ó kù láti Gbà

1 JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà. 2 Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri; 3 Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù: 4 Gbogbo ilẹ awọn ara Kenaani, ati Meara ti awọn ara Sidoni, dé Afeki, titi dé àgbegbe awọn Amori: 5 Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati: 6 Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ. 7 Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

Pípín Agbègbè Tí Ó Wà ní Ìlà Oòrùn Odò Jọrdani

8 Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn; 9 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni; 10 Ati gbogbo ilu Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, titi dé àgbegbe awọn ọmọ Ammoni: 11 Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka; 12 Gbogbo ilẹ ọba Ogu ni Baṣani, ti o jọba ni Aṣtarotu ati ni Edrei, ẹniti o kù ninu awọn Refaimu iyokù: nitori awọn wọnyi ni Mose kọlù, ti o si lé jade. 13 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni. 14 Kìki ẹ̀ya Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun; ẹbọ OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti a fi iná ṣe ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Reubẹni

15 Mose si fi fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni, gẹgẹ bi idile wọn. 16 Àla wọn bẹ̀rẹ lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji nì, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ti mbẹ ni ìha Medeba; 17 Heṣboni, ati gbogbo ilu rẹ̀ ti mbẹ ni pẹtẹlẹ̀; Diboni, ati Bamoti-baali, ati Beti-baali-meoni; 18 Ati Jahasa, ati Kedemoti, ati Mefaati; 19 Ati Kiriataimu, ati Sibma, ati Sareti-ṣahari ni òke afonifoji na; 20 Ati Beti-peori, ati orisun Pisga, ati Beti-jeṣimotu; 21 Ati gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, ti Mose kọlù pẹlu awọn ọmọ alade Midiani, Efi, ati Rekemu, ati Suri, ati Huri, ati Reba, awọn ọmọ alade Sihoni, ti ngbé ilẹ na. 22 Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa. 23 Ati àla awọn ọmọ Reubeni ni Jordani, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni ilẹ iní awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi idile wọn, awọn ilu ati ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Gadi

24 Mose si fi ilẹ fun ẹ̀ya Gadi, ani fun awọn ọmọ Gadi, gẹgẹ bi idile wọn. 25 Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba; 26 Ati lati Heṣboni titi dé Ramatu-mispe, ati Betonimu; ati lati Mahanaimu titi dé àgbegbe Debiri; 27 Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn. 28 Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọn ati ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Manase ní ìlà Oòrùn

29 Mose si fi ilẹ-iní fun àbọ ẹ̀ya Manasse: o si jẹ́ ti àbọ ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse gẹgẹ bi idile wọn. 30 Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Mahanaimu lọ, gbogbo Baṣani, gbogbo ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ilu Jairi, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu: 31 Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn. 32 Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn. 33 Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Joṣua 14

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Wà Ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn Odò Jọrdani

1 WỌNYI si ni ilẹ-iní ti awọn ọmọ Israeli gbà ni iní ni ilẹ Kenaani, ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli pín fun wọn, 2 Keké ni nwọn fi ní ilẹ-iní wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá, fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya ni. 3 Nitori Mose ti fi ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya meji ati àbọ ẹ̀ya li apa keji Jordani: ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun lãrin wọn. 4 Nitoripe ẹ̀ya meji ni ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu: nitorina nwọn kò si fi ipín fun awọn ọmọ Lefi ni ilẹ na, bikoṣe ilu lati ma gbé, pẹlu àgbegbe ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn ati ohun-iní wọn. 5 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni awọn ọmọ Israeli ṣe, nwọn si pín ilẹ na.

Wọ́n fún Kalebu ní Hebroni

6 Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea. 7 Ẹni ogoji ọdún ni mi nigbati Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ na; mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi. 8 Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. 9 Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. 10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni. 11 Sibẹ̀ emi lí agbara li oni gẹgẹ bi mo ti ní li ọjọ́ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti ri nigbana, ani bẹ̃li agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle. 12 Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi. 13 Joṣua si sure fun u; o si fi Hebroni fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní. 14 Nitorina Hebroni di ilẹ-iní Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi titi di oni-oloni; nitoriti o tọ̀ OLUWA Ọlọrun Israeli lẹhin patapata. 15 Orukọ Hebroni lailai rí a ma jẹ́ Kiriati-arba; Arba jẹ́ enia nla kan ninu awọn ọmọ Anaki. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.

Joṣua 15

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Juda

1 ILẸ ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn si dé àgbegbe Edomu, ni aginjù Sini, ni ìha gusù, ni apa ipẹkun gusù. 2 Ati àla gusù wọn ni lati eti Okun Iyọ̀ lọ, lati ibi kọ̀rọ omi nì lọ ti o dojukọ ìha gusù: 3 O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka: 4 Lati ibẹ̀ o lọ dé Asmoni, o si nà lọ si odò Egipti; opín ilẹ na si yọ si okun: eyi ni yio jẹ́ àla ni gusù nyin. 5 Ati àla ìha ìla-õrùn ni Okun Iyọ̀, ani titi dé ipẹkun Jordani. Ati àla apa ariwa ni lati kọ̀rọ okun nì wá dé ipẹkun Jordani: 6 Àla na si gòke lọ si Beti-hogla, o si kọja lọ ni ìha ariwa Beti-araba; àla na si gòke lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni: 7 Àla na si gòke lọ si Debiri lati afonifoji Akoru, ati bẹ̃ lọ si ìha ariwa, ti o dojukọ Gilgali, ti mbẹ niwaju òke Adummimu, ti mbẹ ni ìha gusù odò na: àla si kọja si apa omi Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Eni-rogeli: 8 Àla na si gòke lọ si ìha afonifoji ọmọ Hinnomu si ìha gusù ti Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): àla na si gòke lọ si ori òke nla ti mbẹ niwaju afonifoji Hinnomu ni ìha ìwọ-õrùn, ti mbẹ ni ipẹkun afonifoji Refaimu ni ìha ariwa: 9 A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:) 10 Àla na yi lati Baala lọ si ìha ìwọ-õrùn si òke Seiri, o si kọja lọ si ẹba òke Jearimu (ti ṣe Kesaloni), ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Beti-ṣemeṣi, o si kọja lọ si Timna: 11 Àla na si kọja lọ si ẹba Ekroni si ìha ariwa: a si fà àla na lọ dé Ṣikroni, o si kọja lọ si òke Baala, o si yọ si Jabneeli; àla na si yọ si okun. 12 Àla ìwọ-õrùn si dé okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni àla awọn ọmọ Juda yiká kiri gẹgẹ bi idile wọn.

Kalebu Ṣẹgun Heburoni ati Debiri

13 Ati fun Kalebu ọmọ Jefunne li o fi ipín fun lãrin awọn ọmọ Juda, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA fun Joṣua, ani Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni); Arba si ni baba Anaki. 14 Kalebu si lé awọn ọmọ Anaki mẹta kuro nibẹ̀, Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki. 15 O si gòke lati ibẹ̀ tọ̀ awọn ara Debiri lọ: orukọ Debiri lailai rí ni Kiriati-seferi. 16 Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o sì kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. 17 Otnieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. 18 O si ṣe, bi Aksa ti dé ọdọ rẹ̀, o mu u bère ọ̀rọ kan lọwọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? 19 On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.

Àwọn Ìlú Ńláńlá Tí Wọ́n Wà ní Juda

20 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn. 21 Ilu ipẹkun ẹ̀ya awọn ọmọ Juda li àgbegbe Edomu ni Gusù ni Kabseeli, ati Ederi, ati Jaguri; 22 Ati Kina, ati Dimona, ati Adada; 23 Ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Itnani; 24 Sifu, ati Telemu, ati Bealotu; 25 Ati Haṣori-hadatta, ati Keriotu-hesroni (ti iṣe Hasori); 26 Amamu, ati Ṣema, ati Molada; 27 Ati Hasari-gada, ati Heṣmoni, ati Beti-peleti; 28 Ati Hasari-ṣuali, ati Beeri-ṣeba, ati Bisi-otia; 29 Baala, ati Iimu, ati Esemu; 30 Ati Eltoladi, ati Kesili, ati Horma; 31 Ati Siklagi, ati Madmanna, ati Sansanna; 32 Ati Lebaotu, ati Ṣilhimu, ati Aini, ati Rimmoni: gbogbo ilu na jasi mọkandilọgbọ̀n, pẹlu ileto wọn. 33 Ni pẹtẹlẹ̀, Eṣtaoli, ati Sora, ati Aṣna; 34 Ati Sanoa, ati Eni-gannimu Tappua, ati Enamu; 35 Jarmutu, ati Adullamu, Soko, ati Aseka; 36 Ati Ṣaaraimu, ati Aditaimu, ati Gedera, ati Gederotaimu; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. 37 Senani, ati Hadaṣa, ati Migdali-gadi; 38 Ati Dilani, ati Mispe, ati Jokteeli; 39 Lakiṣi, ati Boskati, ati Egloni; 40 Ati Kabboni, ati Lamamu, ati Kitliṣi; 41 Ati Gederotu, Beti-dagoni, ati Naama, ati Makkeda; ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn. 42 Libna, ati Eteri, ati Aṣani; 43 Ati Ifta, ati Aṣna, ati Nesibu; 44 Ati Keila, ati Aksibu, ati Mareṣa; ilu mẹsan pẹlu ileto wọn. 45 Ekroni, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ati awọn ileto rẹ̀: 46 Lati Ekroni lọ ani titi dé okun, gbogbo eyiti mbẹ leti Aṣdodu, pẹlu ileto wọn. 47 Aṣdodu, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; Gasa, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; dé odò Egipti, ati okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. 48 Ati ni ilẹ òke, Ṣamiri, ati Jattiri, ati Soko; 49 Ati Dana, ati Kiriati-sana (ti ṣe Debiri); 50 Ati Anabu, ati Eṣtemo, ati Animu; 51 Ati Goṣeni, ati Holoni, ati Gilo; ilu mọkanla pẹlu ileto wọn. 52 Arabu, ati Duma, ati Eṣani; 53 Ati Janimu, ati Beti-tappua, ati Afeka; 54 Ati Humta, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni), ati Siori; ilu meṣan pẹlu ileto wọn. 55 Maoni, Karmeli, ati Sifu, ati Juta; 56 Ati Jesreeli, ati Jokdeamu, ati Sanoa; 57 Kaini, Gibea, ati Timna; ilu mẹwa pẹlu ileto wọn. 58 Halhulu, Beti-suru, ati Gedori; 59 Ati Maarati, ati Beti-anotu, ati Eltekoni; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn. 60 Kiriati-baali (ti iṣe Kiriati-jearimu), ati Rabba; ilu meji pẹlu ileto wọn. 61 Li aginjù, Beti-araba, Middini, ati Sekaka; 62 Ati Nibṣani, ati Ilu Iyọ̀, ati Eni-gedi; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn. 63 Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.

Joṣua 16

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli; 2 O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu; 3 O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun. 4 Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.

Efraimu

5 Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke; 6 Àla na si lọ si ìha ìwọ-õrùn si ìha ariwa Mikmeta; àla na si yi lọ si ìha ìla-õrùn dé Taanati-ṣilo, o si kọja lẹba rẹ̀ lọ ni ìha ìla-õrùn Janoha; 7 O si sọkalẹ lati Janoha lọ dé Atarotu, ati dé Naara, o si dé Jeriko, o si yọ si Jordani. 8 Àla na jade lọ lati Tappua si ìha ìwọ-õrùn titi dé odò Kana; o si yọ si okun. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn; 9 Pẹlu ilu ti a yàsọtọ fun awọn ọmọ Efraimu lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Manasse, gbogbo ilu na pẹlu ileto wọn. 10 Nwọn kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade: ṣugbọn awọn ara Kenaani joko lãrin Efraimu titi di oni yi, nwọn si di ẹrú lati ma sìnru.

Joṣua 17

Ilẹ̀ Ẹ̀yà Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani. 2 Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn. 3 Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa. 4 Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA. 5 Ipín mẹwa si bọ́ sọdọ Manasse, làika ilẹ Gileadi ati Baṣani, ti mbẹ ni ìha keji Jordani; 6 Nitoriti awọn ọmọbinrin Manasse ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin: awọn ọmọ Manasse ọkunrin iyokù si ní ilẹ Gileadi. 7 Àla Manasse si lọ lati Aṣeri dé Mikmeta, ti mbẹ niwaju Ṣekemu; àla na si lọ titi ni ìha ọtún, sọdọ awọn ara Eni-tappua. 8 Manasse li o ní ilẹ Tappua: ṣugbọn Tappua li àla Manasse jẹ́ ti awọn ọmọ Efraimu. 9 Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun: 10 Ni ìha gusù ti Efraimu ni, ati ni ìha ariwa ti Manasse ni, okun si ni àla rẹ̀; nwọn si dé Aṣeri ni ìha ariwa, ati Issakari ni ìha ìla-õrùn. 11 Manasse si ní ni Issakari ati ni Aṣeri, Beti-ṣeani ati awọn ilu rẹ̀, ati Ibleamu ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Dori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Enidori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Taanaki ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megiddo ati awọn ilu rẹ̀, ani òke mẹta na. 12 Ṣugbọn awọn ọmọ Manasse kò le gbà ilu wọnyi; awọn ara Kenaani si ngbé ilẹ na. 13 O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli ndi alagbara, nwọn mu awọn ara Kenaani sìn, ṣugbọn nwọn kò lé wọn jade patapata.

Ẹ̀yà Efraimu ati ti Manase ti Ìwọ̀ Oòrùn Bèèrè fún Ilẹ̀ Sí i

14 Awọn ọmọ Josefu si wi fun Joṣua pe, Ẽṣe ti iwọ fi fun mi ni ilẹ kan, ati ipín kan ni ilẹ-iní, bẹ̃ni enia nla ni mi, niwọnbi OLUWA ti bukún mi titi di isisiyi? 15 Joṣua si da wọn lohùn pe, Bi iwọ ba jẹ́ enia nla, gòke lọ si igbó, ki o si ṣanlẹ fun ara rẹ nibẹ̀ ni ilẹ awọn Perissi ati ti Refaimu; bi òke Efraimu ba há jù fun ọ. 16 Awọn ọmọ Josefu si wipe, Òke na kò to fun wa: gbogbo awọn ara Kenaani ti ngbé ilẹ afonifoji si ní kẹkẹ́ irin, ati awọn ti mbẹ ni Beti-ṣeani, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ti mbẹ ni afonifoji Jesreeli. 17 Joṣua si wi fun ile Josefu, ani fun Efraimu ati fun Manasse pe, Enia nla ni iwọ, iwọ si lí agbara pipọ̀: iwọ ki yio ní ipín kanṣoṣo: 18 Ṣugbọn ilẹ òke yio jẹ́ tirẹ; nitoriti iṣe igbó, iwọ o si ṣán a, ati ìna rẹ̀ yio jẹ́ tirẹ: nitoriti iwọ o lé awọn ara Kenaani jade, bi o ti jẹ́ pe nwọn ní kẹkẹ́ irin nì, ti o si jẹ́ pe nwọn lí agbara.

Joṣua 18

Pípín Ilẹ̀ Yòókù

1 GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn. 2 Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn. 3 Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin? 4 Ẹ yàn ọkunrin mẹta fun ẹ̀ya kọkan: emi o si rán wọn, nwọn o si dide, nwọn o si là ilẹ na já, nwọn o si ṣe apejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ilẹ-iní wọn; ki nwọn ki o si pada tọ̀ mi wá. 5 Nwọn o si pín i si ọ̀na meje: Juda yio ma gbé ilẹ rẹ̀ ni gusù, ile Josefu yio si ma gbé ilẹ wọn ni ariwa. 6 Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa. 7 Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn. 8 Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo. 9 Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo. 10 Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Bẹnjamini

11 Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu. 12 Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni. 13 Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ. 14 A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn. 15 Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa: 16 Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli; 17 A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni; 18 O si kọja lọ si apa ibi ti o kọjusi Araba ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Araba: 19 Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù. 20 Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn. 21 Njẹ ilu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn, ni Jeriko, ati Beti-hogla, ati Emekikesisi; 22 Ati Beti-araba, ati Semaraimu, ati Beti-eli; 23 Ati Affimu, ati Para, ati Ofra; 24 Ati Kefari-ammoni, ati Ofni, ati Geba; ilu mejila pẹlu ileto wọn: 25 Gibeoni, ati Rama, ati Beerotu; 26 Ati Mispe, ati Kefira, ati Mosa; 27 Ati Rekemu, ati Irpeeli, ati Tarala; 28 Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.

Joṣua 19

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Simeoni

1 IPÍN keji yọ fun Simeoni, ani fun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn; ilẹ-iní wọn si wà lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Juda. 2 Nwọn si ní Beeri-ṣeba, tabi Ṣeba, ati Molada, ni ilẹ-iní wọn; 3 Ati Hasari-ṣuali, ati Bala, ati Esemu; 4 Ati Eltoladi, ati Bẹtulu, ati Horma; 5 Ati Siklagi, ati Beti-markabotu, ati Hasari-susa; 6 Ati Beti-lebaotu, ati Ṣaruheni; ilu mẹtala pẹlu ileto wọn: 7 Aini, Rimmoni, ati Eteri, ati Aṣani; ilu mẹrin pẹlu ileto wọn: 8 Ati gbogbo ileto ti o yi ilu wọnyi ká dé Baalati-beeri, Rama ti Gusù. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn. 9 Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Sebuluni

10 Ilẹ kẹta yọ fun awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: àla ilẹ-iní wọn si dé Saridi: 11 Àla wọn gòke lọ si ìha ìwọ-õrùn, ani titi o fi dé Marala, o si dé Dabaṣeti; o si dé odò ti mbẹ niwaju Jokneamu; 12 O si ṣẹri lati Saridi lọ ni ìha ìla-õrùn si ìla-õrùn dé àla Kisloti-tabori; o si yọ si Daberati; o si jade lọ si Jafia; 13 Ati lati ibẹ̀ o kọja ni ìha ìla-õrùn si Gati-heferi, dé Ẹti-kasini; o si yọ si Rimmoni titi o fi dé Nea; 14 Àla na si yi i ká ni ìha ariwa dé Hannatoni: o si yọ si afonifoji Ifta-eli; 15 Ati Katati, ati Nahalali, ati Ṣimroni, ati Idala, ati Beti-lehemu: ilu mejila pẹlu ileto wọn. 16 Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Isakari

17 Ipín kẹrin yọ fun Issakari, ani fun awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn. 18 Àla wọn si dé Jesreeli, ati Kesuloti, ati Ṣunemu; 19 Ati Hafaraimu, ati Ṣihoni, ati Anaharati; 20 Ati Rabbiti, Kiṣioni, ati Ebesi; 21 Ati Remeti, ati Eni-gannimu, ati Enhadda, ati Beti-passesi; 22 Àla na si dé Tabori, ati Ṣahasuma, ati Beti-ṣemeṣi; àla wọn yọ si Jordani: ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn. 23 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi ati ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Aṣeri

24 Ipín karun yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn. 25 Àla wọn si ni Helkati, ati Hali, ati Beteni, ati Akṣafu; 26 Ati Allammeleki, ati Amadi, ati Miṣali; o si dé Karmeli ni ìha ìwọ-õrùn, ati Ṣihorilibnati; 27 O si ṣẹri lọ si ìha ìla-õrùn dé Beti-dagoni, o si dé Sebuluni, ati afonifoji Ifta-eli ni ìha ariwa dé Betemeki, ati Neieli; o si yọ si Kabulu li apa òsi, 28 Ati Ebroni, ati Rehobu, ati Hammoni, ati Kana, ani titi dé Sidoni nla; 29 Àla na si ṣẹri lọ si Rama, ati si Tire ilu olodi; àla na si ṣẹri lọ si Hosa; o si yọ si okun ni ìha Aksibu: 30 Ati Umma, ati Afeki, ati Rehobu: ilu mejilelogun pẹlu ileto wọn. 31 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Naftali

32 Ipín kẹfa yọ fun awọn ọmọ Naftali, ani fun awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn. 33 Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Helefu, lati igi-oaku Saanannimu, ati Adami-nekebu, ati Jabneeli dé Lakkumu; o si yọ si Jordani. 34 Àla na si ṣẹri lọ sí ìha ìwọ-õrùn si Asnoti-taboru, o si ti ibẹ̀ lọ si Hukkoki; o si dé Sebuluni ni gusù, o si dé Aṣeri ni ìwọ-õrùn, ati Juda ni Jordani ni ìha ìla-õrùn. 35 Awọn ilu olodi si ni Siddimu, Seri, ati Hammati, Rakkati, ati Kinnereti; 36 Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru; 37 Ati Kedeṣi, ati Edrei, ati Eni-hasoru; 38 Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn. 39 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Dani

40 Ilẹ keje yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn. 41 Àla ilẹ-iní wọn si ni Sora, ati Eṣtaolu, ati Iri-ṣemeṣi; 42 Ati Ṣaalabbini, ati Aijaloni, ati Itla; 43 Ati Eloni, ati Timna, ati Ekroni; 44 Ati Elteke, ati Gibbetoni, ati Baalati; 45 Ati Jehudi, ati Bene-beraki, ati Gati-rimmọni; 46 Ati Me-jarkoni, ati Rakkoni, pẹlu àla ti mbẹ kọjusi Jọppa. 47 Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn. 48 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Kù

49 Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn: 50 Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA, nwọn fun u ni ilu ti o bère, ani Timnati-sera li òke Efraimu: o si kọ ilu na, o si ngbé inu rẹ̀. 51 Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.

Joṣua 20

Àwọn Ìlú Ààbò

1 OLUWA si sọ fun Joṣua pe, 2 Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ yàn ilu àbo fun ara nyin, ti mo ti sọ fun nyin lati ọwọ́ Mose wa: 3 Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ. 4 On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé. 5 Bi olugbẹsan ẹ̀jẹ ba lepa rẹ̀, njẹ ki nwọn ki o má ṣe fi apania na lé e lọwọ; nitoriti o pa aladugbo rẹ̀ li aimọ̀, ti kò si korira rẹ̀ tẹlẹrí. 6 On o si ma gbé inu ilu na, titi yio fi duro niwaju ijọ fun idajọ, titi ikú olori alufa o wà li ọjọ́ wọnni: nigbana ni apania na yio pada, on o si wá si ilu rẹ̀, ati si ile rẹ̀, si ilu na lati ibiti o gbé ti salọ. 7 Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda. 8 Ati ni ìha keji Jordani lẹba Jeriko ni ìla-õrùn, nwọn yàn Beseri li aginjù ni pẹtẹlẹ̀ ninu ẹ̀ya Reubeni, ati Ramotu ni Gileadi ninu ẹ̀ya Gadi, ati Golani ni Baṣani ninu ẹ̀ya Manasse. 9 Wọnyi ni awọn ilu ti a yàn fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo lãrin wọn, ki ẹnikẹni ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan, ki o le salọ sibẹ̀, ki o má ba si ti ọwọ́ olugbẹsan ẹ̀jẹ ku, titi on o fi duro niwaju ijọ.

Joṣua 21

Ìlú Àwọn Ọmọ Lefi

1 NIGBANA ni awọn olori awọn baba awọn ọmọ Lefi sunmọ Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; 2 Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa. 3 Awọn ọmọ Israeli si fi ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn fun awọn ọmọ Lefi ninu ilẹ-iní wọn, nipa aṣẹ OLUWA. 4 Ipín si yọ fun idile awọn ọmọ Kohati: ati awọn ọmọ Aaroni alufa, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu ẹ̀ya Juda, ati lati inu ẹ̀ya Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya Benjamini. 5 Awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Kohati, fi keké gbà ilu mẹwa lati inu idile ẹ̀ya Efraimu, ati lati inu ẹ̀ya Dani, ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse. 6 Awọn ọmọ Gerṣoni si fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu idile ẹ̀ya Issakari, ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati inu àbọ ẹ̀ya Manasse ni Baṣani. 7 Awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn, ní ilu mejila, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni. 8 Awọn ọmọ Israeli fi keké fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá. 9 Nwọn si fi ilu ti a darukọ wọnyi fun wọn, lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni wá: 10 Nwọn si jẹ́ ti awọn ọmọ Aaroni, ni idile awọn ọmọ Kohati, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, nitoriti nwọn ní ipín ikini. 11 Nwọn si fi Kiriati-arba, ti iṣe Hebroni fun wọn, (Arba ni baba Anaki ni ilẹ òke Juda,) pẹlu àgbegbe rẹ̀ yi i kakiri. 12 Ṣugbọn pápa ilu na, ati ileto rẹ̀, ni nwọn fi fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní rẹ̀. 13 Nwọn si fi Hebroni ilu àbo fun apania pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Libna pẹlu àgbegbe rẹ̀, fun awọn ọmọ Aaroni alufa; 14 Ati Jatiri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Eṣtemoa pẹlu àgbegbe rẹ̀; 15 Ati Holoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Debiri pẹlu àgbegbe rẹ̀; 16 Ati Aini pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jutta pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-ṣemeṣi pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹsan ninu awọn ẹ̀ya meji wọnni. 17 Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini, Gibeoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Geba pẹlu àgbegbe rẹ̀; 18 Anatotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Almoni pelu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 19 Gbogbo ilu awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu àgbegbe wọn. 20 Ati idile awọn ọmọ Kohati, awọn ọmọ Lefi, ani awọn ọmọ Kohati ti o kù, nwọn ní ilu ti iṣe ipín ti wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu. 21 Nwọn si fi Ṣekemu fun wọn pẹlu àgbegbe rẹ̀, ni ilẹ òke Efraimu, ilu àbo fun apania, ati Geseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; 22 Ati Kibsaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-horoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 23 Ati ninu ẹ̀ya Dani, Elteke pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gibbetoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; 24 Aijaloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 25 Ati ninu àbọ ẹ̀ya Manasse, Taanaki pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. 26 Gbogbo ilu na jasi mẹwa pẹlu àgbegbe wọn fun idile awọn ọmọ Kohati ti o kù. 27 Ati awọn ọmọ Gerṣoni, idile awọn ọmọ Lefi, ni nwọn fi Golani ni Baṣani fun pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; lati inu ẹ̀ya Manasse, ati Be-eṣtera pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. 28 Ati ninu ẹ̀ya Issakari, Kiṣioni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Dabarati pẹlu àgbegbe rẹ̀; 29 Jarmutu pẹlu àgbegbe rẹ̀, Engannimu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 30 Ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, Miṣali pẹlu àgbegbe rẹ̀, Abdoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; 31 Helkati pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Rehobu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 32 Ati lati inu ẹ̀ya Naftali, Kedeṣi ni Galili pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Hammotu-dori pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Kartani pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹta. 33 Gbogbo ilu awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu ileto wọn. 34 Ati fun idile awọn ọmọ Merari, awọn ọmọ Lefi ti o kù, ni Jokneamu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Karta pẹlu àgbegbe rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni, 35 Dimna pẹlu àgbegbe rẹ̀, Nahalali pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 36 Ati ninu ẹ̀ya Reubeni, Beseri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jahasi pẹlu àgbegbe rẹ̀, 37 Kedemotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Mefaati pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. 38 Ati ninu ẹ̀ya Gadi, Ramotu ni Gileadi pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Mahanaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀. 39 Heṣboni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Jaseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin ni gbogbo rẹ̀. 40 Gbogbo wọnyi ni ilu awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi idile wọn, ani awọn ti o kù ni idile awọn ọmọ Lefi; ipín wọn si jẹ́ ilu mejila. 41 Gbogbo ilu awọn ọmọ Lefi ti mbẹ lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli jẹ́ ilu mejidilãdọta pẹlu àgbegbe wọn. 42 Olukuluku ilu wọnyi li o ní àgbegbe wọn yi wọn ká: bayi ni gbogbo ilu wọnyi ri.

Israẹli Gba Ilẹ̀ náà

43 OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀. 44 OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ. 45 Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ.

Joṣua 22

Joṣua Dá Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Pada Sílé

1 NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, 2 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin: 3 Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin. 4 Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani. 5 Kìki ki ẹ kiyesara gidigidi lati pa aṣẹ ati ofin mọ́, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin, lati fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati lati faramọ́ ọ, ati lati sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo. 6 Bẹ̃ni Joṣua sure fun wọn, o si rán wọn lọ: nwọn si lọ sinu agọ́ wọn. 7 Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu, 8 O si wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ pẹlu ọrọ̀ pipọ̀ si agọ́ nyin, ati pẹlu ohunọ̀sin pipọ̀, pẹlu fadakà, ati pẹlu wurà, ati pẹlu idẹ ati pẹlu irin, ati pẹlu aṣọ pipọ̀pipọ: ẹ bá awọn arakunrin nyin pín ikogun awọn ọtá nyin. 9 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.

Pẹpẹ Tí Ó Wà Lẹ́bàá Odò Jọrdani

10 Nigbati nwọn si dé eti Jordani, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan lẹba Jordani, pẹpẹ ti o tobi lati wò. 11 Awọn ọmọ Israeli si gbọ́ pe, Kiyesi i, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan dojukọ ilẹ Kenaani, lẹba Jordani ni ìha keji awọn ọmọ Israeli. 12 Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli kó ara wọn jọ ni Ṣilo, lati gòke lọ ibá wọn jagun. 13 Awọn ọmọ Israeli si rán Finehasi ọmọ Eleasari alufa si awọn ọmọ Reubeni, ati si awọn ọmọ Gadi, ati si àbọ ẹ̀ya Manasse ni ilẹ Gileadi; 14 Ati awọn olori mẹwa pẹlu rẹ̀, olori ile baba kọkan fun gbogbo ẹ̀ya Israeli; olukuluku si ni olori ile baba wọn ninu ẹgbẹgbẹrun Israeli. 15 Nwọn si dé ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ati ọdọ àbọ ẹ̀ya Manasse, ni ilẹ Gileadi, nwọn si bá wọn sọ̀rọ pe, 16 Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni? 17 Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA, 18 Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli. 19 Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa. 20 Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 21 Nigbana ni awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse dahùn, nwọn si wi fun awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli pe, 22 OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ̀, Israeli pẹlu yio si mọ̀; bi o ba ṣepe ni ìṣọtẹ ni, tabi bi ni irekọja si OLUWA, (má ṣe gbà wa li oni,) 23 Ni awa fi mọ pẹpẹ fun ara wa, lati yipada kuro lẹhin OLUWA; tabi bi o ba ṣe pe lati ru ẹbọ sisun, tabi ẹbọ ohunjijẹ, tabi ẹbọ alafia lori rẹ̀, ki OLUWA tikala rẹ̀ ki o bère rẹ̀. 24 Bi o ba ṣepe awa kò kuku ṣe e nitori aniyàn, ati nitori nkan yi pe, Lẹhinọla awọn ọmọ nyin le wi fun awọn ọmọ wa pe, Kili o kàn nyin niti OLUWA, Ọlọrun Israeli? 25 Nitoriti Ọlọrun ti fi Jordani pàla li agbedemeji awa ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi; ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA: bẹ̃li awọn ọmọ nyin yio mu ki awọn ọmọ wa ki o dẹkun ati ma bẹ̀ru OLUWA. 26 Nitorina li a ṣe wipe, Ẹ jẹ ki a mura nisisiyi lati mọ pẹpẹ kan, ki iṣe fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan: 27 Ṣugbọn ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin, ati awọn iran wa lẹhin wa, ki awa ki o le ma fi ẹbọ sisun wa, ati ẹbọ wa, pẹlu ẹbọ alafia wa jọsìn fun OLUWA niwaju rẹ̀; ki awọn ọmọ nyin ki o má ba wi fun awọn ọmọ wa lẹhinọla pe, Ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA. 28 Nitorina ni awa ṣe wipe, Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi bẹ̃ fun wa, tabi fun awọn iran wa lẹhinọla, awa o si wipe, Ẹ wò apẹrẹ pẹpẹ OLUWA, ti awọn baba wa mọ, ki iṣe fun ẹbọ sisun, bẹ̃ni ki iṣe fun ẹbọ; ṣugbọn o jasi ẹrí li agbedemeji awa ati ẹnyin. 29 Ki Ọlọrun má jẹ ki awa ki o ṣọ̀tẹ si OLUWA, ki awa si pada li oni kuro lẹhin OLUWA, lati mọ pẹpẹ fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ ohunjije, tabi fun ẹbọ kan, lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa ti mbẹ niwaju agọ́ rẹ̀. 30 Nigbati Finehasi alufa, ati awọn olori ijọ, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli ti o wà pẹlu rẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati awọn ọmọ Manasse sọ, o dùnmọ́ wọn. 31 Finehasi ọmọ Eleasari alufa si wi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Manasse pe, Li oni li awa mọ̀ pe OLUWA wà lãrin wa, nitoriti ẹnyin kò dẹ̀ṣẹ yi si OLUWA: nisisiyi ẹnyin yọ awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ OLUWA. 32 Finehasi ọmọ Eleasari alufa, ati awọn olori, si pada lati ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati lati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ni ilẹ Gileadi, si ilẹ Kenaani, sọdọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si mú ìhin pada tọ̀ wọn wá. 33 Ohun na si dùnmọ́ awọn ọmọ Israeli; awọn ọmọ Israeli si fi ibukún fun Ọlọrun, nwọn kò si sọ ti ati gòke tọ̀ wọn lọ ijà, lati run ilẹ na ninu eyiti awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ngbé. 34 Awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi si sọ pẹpẹ na ni Edi: nwọn wipe, Nitori ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin pe OLUWA on li Ọlọrun.

Joṣua 23

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Tí Joṣua Sọ

1 O si ṣe li ọjọ́ pipọ̀ lẹhin ti OLUWA ti fi isimi fun Israeli lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn yiká, ti Joṣua di arugbó, ti o si pọ̀ li ọjọ́; 2 Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́: 3 Ẹnyin si ti ri ohun gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si gbogbo orilẹ-ède wọnyi nitori nyin; nitori OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti o ti jà fun nyin. 4 Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn. 5 OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio tì wọn jade kuro niwaju nyin, yio si lé wọn kuro li oju nyin; ẹnyin o si ní ilẹ wọn, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin. 6 Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi; 7 Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn: 8 Ṣugbọn ki ẹnyin faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe titi di oni. 9 Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni. 10 ọkunrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin. 11 Nitorina ẹ kiyesara nyin gidigidi, ki ẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin. 12 Ṣugbọn bi ẹ ba daṣà ati pada, ti ẹ si faramọ́ iyokù awọn orile-ède wọnyi, ani awọn wọnyi ti o kù lãrin nyin, ti ẹ si bá wọn gbeyawo, ti ẹ si nwọle tọ̀ wọn, ti awọn si nwọle tọ̀ nyin: 13 Ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe OLUWA Ọlọrun nyin ki yio lé awọn orilẹ-ède wọnyi jade mọ́ kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ okùn-didẹ ati ẹgẹ́ fun nyin, ati paṣán ni ìha nyin, ati ẹgún li oju nyin, titi ẹ o fi ṣegbé kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin. 14 Ẹnyin kiyesi i, li oni emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: ényin si mọ̀ li àiya nyin gbogbo, ati li ọkàn nyin gbogbo pe, kò sí ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ fun nyin, kò si sí ohun ti o tase ninu rẹ̀. 15 Yio si ṣe, gẹgẹ bi ohun rere gbogbo ti ṣẹ fun nyin, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin; bẹ̃ni OLUWA yio mú ibi gbogbo bá nyin, titi yio fi pa nyin run kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin. 16 Nigbati ẹnyin ba re majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin kọja, ti o palaṣẹ fun nyin, ti ẹ ba si lọ, ti ẹ ba nsìn oriṣa ti ẹnyin ba tẹ̀ ori nyin bà fun wọn; nigbana ni ibinu OLUWA yio rú si nyin, ẹnyin o si ṣegbé kánkan kuro ni ilẹ daradara ti o ti fi fun nyin.

Joṣua 24

Joṣua Bá Àwọn Eniyan náà Sọ̀rọ̀ ní Ṣekemu

1 JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun. 2 Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa. 3 Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki. 4 Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti. 5 Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade. 6 Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa. 7 Nigbati nwọn kigbepè OLUWA, o fi òkunkun si agbedemeji ẹnyin ati awọn ara Egipti, o si mú okun ya lù wọn, o si bò wọn mọlẹ; oju nyin si ti ri ohun ti mo ṣe ni Egipti: ẹnyin si gbé inu aginjù li ọjọ́ pipọ̀. 8 Emi si mú nyin wá si ilẹ awọn Amori, ti ngbé ìha keji Jordani; nwọn si bá nyin jà: emi si fi wọn lé nyin lọwọ ẹnyin si ní ilẹ wọn; emi si run wọn kuro niwaju nyin. 9 Nigbana ni Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu dide, o si ba Israeli jagun; o si ranṣẹ pè Balaamu ọmọ Beori lati fi nyin bú: 10 Ṣugbọn emi kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; nitorina o nsure fun nyin ṣá: mo si gbà nyin kuro li ọwọ́ rẹ̀. 11 Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ. 12 Emi si rán agbọ́n siwaju nyin, ti o lé wọn kuro niwaju nyin, ani awọn ọba Amori meji; ki iṣe pẹlu idà rẹ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu ọrun rẹ. 13 Emi si fun nyin ni ilẹ ti iwọ kò ṣe lãla si, ati ilu ti ẹnyin kò tẹ̀dó, ẹnyin si ngbé inu wọn; ninu ọgbà-àjara ati ọgbà-igi-olifi ti ẹnyin kò gbìn li ẹnyin njẹ. 14 Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA. 15 Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn. 16 Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa; 17 Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja: 18 OLUWA si lé gbogbo awọn enia na jade kuro niwaju wa, ani awọn Amori ti ngbé ilẹ na: nitorina li awa pẹlu o ṣe ma sìn OLUWA; nitori on li Ọlọrun wa. 19 Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Enyin kò le sìn OLUWA; nitoripe Ọlọrun mimọ́ li on; Ọlọrun owú li on; ki yio dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin. 20 Bi ẹnyin ba kọ̀ OLUWA silẹ, ti ẹ ba si sìn ọlọrun ajeji, nigbana ni on o pada yio si ṣe nyin ni ibi, yio si run nyin, lẹhin ti o ti ṣe nyin li ore tán. 21 Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, Rárá o; ṣugbọn OLUWA li awa o sìn. 22 Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Ẹnyin li ẹlẹri si ara nyin pe, ẹnyin yàn OLUWA fun ara nyin, lati ma sìn i. Nwọn si wipe, Awa ṣe ẹlẹri. 23 Njẹ nitorina ẹ mu ọlọrun ajeji ti mbẹ lãrin nyin kuro, ki ẹnyin si yi ọkàn nyin si OLUWA Ọlọrun Israeli. 24 Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, OLUWA Ọlọrun wa li awa o ma sìn, ohùn rẹ̀ li awa o si ma gbọ́. 25 Bẹ̃ni Joṣua bá awọn enia na dá majẹmu li ọjọ́ na, o si fi ofin ati ìlana fun wọn ni Ṣekemu. 26 Joṣua si kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwé ofin Ọlọrun, o si mú okuta nla kan, o si gbé e kà ibẹ̀ labẹ igi-oaku kan, ti o wà ni ibi-mimọ́ OLUWA. 27 Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin. 28 Bẹ̃ni Joṣua jọwọ awọn enia na lọwọ lọ, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀.

Joṣua ati Eleasari Kú

29 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún. 30 Nwọn si sin i ni àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnatisera, ti mbẹ ni ilẹ òke Efraimu, ni ìha ariwa òke Gaaṣi. 31 Israeli si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, ti o si mọ̀ gbogbo iṣẹ OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. 32 Egungun Josefu, ti awọn ọmọ Israeli gbé gòke lati Egipti wá, ni nwọn si sin ni Ṣekemu, ni ipín ilẹ ti Jakobu rà lọwọ awọn ọmọ Hamori baba Ṣekemu li ọgọrun owo: o si di ilẹ-iní awọn ọmọ Josefu. 33 Eleasari ọmọ Aaroni si kú; nwọn si sin i li òke Finehasi ọmọ rẹ̀, ti a fi fun u li òke Efraimu.

Onidajọ 1

Àwọn Ẹ̀yà Juda ati ti Simeoni Ṣẹgun Adonibeseki

1 O si ṣe lẹhin ikú Joṣua, ni awọn ọmọ Israeli bère lọdọ OLUWA wipe, Tani yio tète gòke tọ̀ awọn ara Kenaani lọ fun wa, lati bá wọn jà? 2 OLUWA si wipe, Juda ni yio gòke lọ: kiyesi i, emi fi ilẹ̀ na lé e lọwọ. 3 Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ. 4 Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki. 5 Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si bá a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi. 6 Ṣugbọn Adoni-beseki sá; nwọn si lepa rẹ̀, nwọn si mú u, nwọn si ke àtampako ọwọ́ rẹ̀, ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀. 7 Adoni-beseki si wipe, Adọrin ọba li emi ke li àtampako ọwọ́ wọn ati ti ẹsẹ̀ wọn, ti nwọn nṣà onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi emi ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun si san a fun mi. Nwọn si mú u wá si Jerusalemu, o si kú sibẹ̀.

Àwọn Ẹ̀yà Juda Ṣẹgun Jerusalẹmu ati Hebroni

8 Awọn ọmọ Juda si bá Jerusalemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tinabọ ilu na. 9 Lẹhin na awọn ọmọ Juda si sọkalẹ lọ lati bá awọn ara Kenaani jà, ti ngbé ilẹ òke, ati ni Gusù, ati ni afonifoji nì. 10 Juda si tọ̀ awọn ara Kenaani ti ngbé Hebroni lọ: (orukọ Hebroni ni ìgba iṣaju si ni Kiriati-arba:) nwọn si pa Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai.

Otnieli Ṣẹgun Ìlú Debiri

11 Lati ibẹ̀ o si gbé ogun tọ̀ awọn ara Debiri lọ. (Orukọ Debiri ni ìgba atijọ si ni Kiriati-seferi.) 12 Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. 13 Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. 14 O si ṣe, nigbati Aksa dé ọdọ rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati bère oko kan lọdọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ kuro lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? 15 On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u.

Ìṣẹgun Àwọn Ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini

16 Awọn ọmọ Keni, ana Mose, si bá awọn ọmọ Juda gòke lati ilu ọpẹ lọ si aginjù Juda, ni gusù Aradi; nwọn si lọ, nwọn si mbá awọn enia na gbé. 17 Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si pa a run patapata. A si pè orukọ ilu na ni Horma. 18 Juda si kó Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Aṣkeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀. 19 OLUWA si wà pẹlu Juda; o si gbà ilẹ òke; nitori on kò le lé awọn enia ti o wà ni pẹtẹlẹ̀ jade, nitoriti nwọn ní kẹkẹ́ irin. 20 Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: on si lé awọn ọmọ Anaki mẹtẹta jade kuro nibẹ̀. 21 Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni.

Àwọn Ẹ̀yà Efraimu ati Ẹ̀yà Manase Ṣẹgun Bẹtẹli

22 Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn. 23 Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.) 24 Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ. 25 O si fi ọ̀na atiwọ̀ ilu na hàn wọn, nwọn si fi oju idà kọlù ilu na; ṣugbọn nwọn jọwọ ọkunrin na ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀ lọwọ lọ. 26 Ọkunrin na si lọ si ilẹ awọn Hitti, o si tẹ̀ ilu kan dó, o si pè orukọ rẹ̀ ni Lusi: eyi si li orukọ rẹ̀ titi di oni.

Àwọn Tí Àwọn Ọmọ Israẹli Kò Lé Jáde

27 Manasse kò si lé awọn ara Beti-seani ati ilu rẹ̀ wọnni jade, tabi awọn ara Taanaki ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Dori ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Ibleamu ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Megiddo ati ilu rẹ̀ wọnni: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na. 28 O si ṣe, nigbati Israeli di alagbara tán, nwọn si mu awọn ara Kenaani sìn, nwọn kò si lé wọn jade patapata. 29 Efraimu kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn ni Geseri. 30 Sebuluni kò lé awọn ara Kitroni jade, tabi awọn ara Nahalolu; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn, nwọn si nsìn. 31 Aṣeri kò lé awọn ara Akko jade, tabi awọn ara Sidoni, tabi awọn ara Alabu, tabi awọn ara Aksibu, tabi awọn ara Helba, tabi awọn ara Afiki, tabi awọn ara Rehobu: 32 Ṣugbọn awọn ọmọ Aṣeri ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: nitoriti nwọn kò lé wọn jade. 33 Naftali kò lé awọn ara Beti-ṣemeṣi jade, tabi awọn ara Beti-anati; ṣugbọn on ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: ṣugbọn awọn ara Beti-ṣemeṣi ati Beti-anati di ẹniti nsìn wọn. 34 Awọn Amori si fi agbara tì awọn ọmọ Dani sori òke: nitoripe nwọn kò jẹ ki nwọn ki o sọkalẹ wá si afonifoji. 35 Awọn Amori si ngbé òke Heresi, ni Aijaloni, ati ni Ṣaalbimu: ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹniti nsìn. 36 Àla awọn Amori si ni lati ìgoke lọ si Akrabbimu, lati ibi apata lọ si òke.

Onidajọ 2

Angẹli OLUWA ní Bokimu

1 ANGELI OLUWA si ti Gilgali gòke wá si Bokimu. O si wipe, Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ ti emi ti bura fun awọn baba nyin; emi si wipe, Emi ki yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai: 2 Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn mi: Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi? 3 Nitorina emi pẹlu wipe, Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ ẹgún ni ìha nyin, ati awọn oriṣa wọn yio di ikẹkun fun nyin. 4 O si ṣe, nigbati angeli OLUWA sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun. 5 Nwọn si pè orukọ ibẹ̀ na ni Bokimu: nwọn si ru ẹbọ nibẹ̀ si OLUWA.

Ikú Joṣua

6 Nigbati Joṣua si ti jọwọ awọn enia lọwọ lọ, olukuluku awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ilẹ-iní rẹ̀ lati gba ilẹ̀ na. 7 Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, awọn ẹniti o ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. 8 Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA si kú, nigbati o di ẹni ãdọfa ọdún. 9 Nwọn si sinkú rẹ̀ li àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnati-heresi, ni ilẹ òke Efraimu, li ariwa oke Gaaṣi. 10 Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli.

Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA

11 Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu: 12 Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu. 13 Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu. 14 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn. 15 Nibikibi ti nwọn ba jade lọ, ọwọ́ OLUWA wà lara wọn fun buburu, gẹgẹ bi OLUWA ti wi, ati gẹgẹ bi OLUWA ti bura fun wọn: oju si pọ́n wọn pupọ̀pupọ̀. 16 OLUWA si gbé awọn onidajọ dide, ti o gbà wọn li ọwọ́ awọn ẹniti nkó wọn lẹrù. 17 Sibẹ̀sibẹ nwọn kò fetisi ti awọn onidajọ wọn, nitoriti nwọn ṣe panṣaga tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, nwọn si fi ori wọn balẹ fun wọn: nwọn yipada kánkan kuro li ọ̀na ti awọn baba wọn ti rìn, ni gbigbà ofin OLUWA gbọ́; awọn kò ṣe bẹ̃. 18 Nigbati OLUWA ba si gbé awọn onidajọ dide fun wọn, OLUWA a si wà pẹlu onidajọ na, on a si gbà wọn kuro li ọwọ́ awọn ọtá wọn ni gbogbo ọjọ́ onidajọ na: nitoriti OLUWA kãnu, nitori ikerora wọn nitori awọn ti npọ́n wọn loju, ti nwọn si nni wọn lara. 19 O si ṣe, nigbati onidajọ na ba kú, nwọn a si pada, nwọn a si bà ara wọn jẹ́ jù awọn baba wọn lọ, ni titọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma fi ori balẹ fun wọn; nwọn kò dẹkun iṣe wọn, ati ìwa-agidi wọn. 20 Ibinu OLUWA si rú si Israeli; o si wipe, Nitoriti orilẹ-ède yi ti re majẹmu mi kọja eyiti mo ti palaṣẹ fun awọn baba wọn, ti nwọn kò si gbọ́ ohùn mi; 21 Emi pẹlu ki yio lé ọkan jade mọ́ kuro niwaju wọn ninu awọn orilẹ-ède, ti Joṣua fisilẹ nigbati o kú: 22 Ki emi ki o le ma fi wọn dan Israeli wò, bi nwọn o ma ṣe akiyesi ọ̀na OLUWA lati ma rìn ninu rẹ̀, bi awọn baba wọn ti ṣe akiyesi rẹ̀, tabi bi nwọn ki yio ṣe e. 23 OLUWA si fi orilẹ-ède wọnni silẹ, li ailé wọn jade kánkan; bẹ̃ni kò si fi wọn lé Joṣua lọwọ.

Onidajọ 3

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Ṣẹ́kù lórí Ilẹ̀ Kenaani

1 NJẸ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israeli wò, ani iye awọn ti kò mọ̀ gbogbo ogun Kenaani; 2 Nitori idí yi pe, ki iran awọn ọmọ Israeli ki o le mọ̀, lati ma kọ́ wọn li ogun, ani irú awọn ti kò ti mọ̀ ọ niṣaju rí; 3 Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati. 4 Wọnyi li a o si ma fi dan Israeli wò, lati mọ̀ bi nwọn o fetisi ofin OLUWA, ti o fi fun awọn baba wọn lati ọwọ́ Mose wá. 5 Awọn ọmọ Israeli si joko lãrin awọn ara Kenaani; ati awọn Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi: 6 Nwọn si fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, nwọn si fi awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọkunrin wọn, nwọn si nsìn awọn oriṣa wọn.

Otnieli

7 Awọn ọmọ Israeli si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nwọn si gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si nsìn Baalimu ati Aṣerotu. 8 Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ. 9 Nigbati awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun awọn ọmọ Israeli, ẹniti o gbà wọn, ani Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu. 10 Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu. 11 Ilẹ na si simi li ogoji ọdún. Otnieli ọmọ Kenasi si kú.

Ehudu

12 Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA. 13 O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ. 14 Awọn ọmọ Israeli si sìn Egloni ọba Moabu li ọdún mejidilogun. 15 Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu. 16 Ehudu si rọ idà kan olojumeji, igbọnwọ kan ni gigùn; on si sán a si abẹ aṣọ rẹ̀ ni itan ọtún. 17 O si mú ọrẹ na wá fun Egloni ọba Moabu; Egloni si jẹ́ ọkunrin ti o sanra pupọ̀. 18 Nigbati o si fi ọrẹ na fun u tán, o rán awọn enia ti o rù ọrẹ na pada lọ. 19 Ṣugbọn on tikara rẹ̀ pada lati ibi ere finfin ti o wà leti Gilgali, o si wipe, Ọba, mo lí ọ̀rọ ìkọkọ kan ibá ọ sọ. On si wipe, Ẹ dakẹ. Gbogbo awọn ẹniti o duro tì i si jade kuro lọdọ rẹ̀. 20 Ehudu si tọ̀ ọ wá; on si nikan joko ninu yará itura rẹ̀. Ehudu si wipe, Mo lí ọ̀rọ kan lati ọdọ Ọlọrun wá fun ọ. On si dide kuro ni ibujoko rẹ̀. 21 Ehudu si nà ọwọ́ òsi rẹ̀, o si yọ idà na kuro ni itan ọtún rẹ̀, o si fi gún u ni ikùn: 22 Ati idà ati ekù si wọle; ọrá si bò idà na nitoriti kò fà idà na yọ kuro ninu ikun rẹ̀; o si yọ lẹhin. 23 Nigbana ni Ehudu si ba ti iloro lọ, o si se ilẹkun gbọngan na mọ́ ọ, o si tì wọn. 24 Nigbati o si jade lọ tán, awọn iranṣẹ rẹ̀ dé; nigbati nwọn wò, si kiyesi i, awọn ilẹkun gbọngan tì; nwọn wipe, Li aisí aniani o bò ẹsẹ̀ rẹ̀ ninu yará itura rẹ̀. 25 Nwọn si duro titi o fi di itiju fun wọn: kiyesi i on kò si ṣí ilẹkun gbọngan na silẹ; nitorina nwọn mú ọmọlẹkun, nwọn si ṣí i: si kiyesi i, oluwa wọn ti ṣubu lulẹ kú. 26 Ehudu si sálọ nigbati nwọn nduro, o si kọja ibi ere finfin, o si sálọ si Seira. 27 O si ṣe, nigbati o dé, o fọn ipè ni ilẹ òke Efraimu, awọn ọmọ Israeli si bá a sọkalẹ lọ lati òke na wá, on si wà niwaju wọn. 28 On si wi fun wọn pe, Ẹ ma tọ̀ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ. Nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ, nwọn si gbà ìwọdo Jordani, ti o wà ni ìha Moabu, nwọn kò si jẹ ki ẹnikan ki o kọja mọ̀. 29 Nwọn si pa ìwọn ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ara Moabu ni ìgba na, gbogbo awọn ti o sigbọnlẹ, ati gbogbo awọn akọni ọkunrin; kò sí ọkunrin kanṣoṣo ti o sálà. 30 Bẹ̃li a tẹ̀ ori Moabu ba ni ijọ́ na li abẹ ọwọ́ Israeli. Ilẹ na si simi li ọgọrin ọdún.

Ṣamgari

31 Lẹhin rẹ̀ ni Ṣamgari ọmọ Anati, ẹniti o fi ọpá ti a fi ndà akọmalu pa ẹgbẹta ọkunrin ninu awọn ara Filistini, on pẹlu si gbà Israeli.

Onidajọ 4

Debora ati Baraki

1 AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nigbati Ehudu kú tán. 2 OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède. 3 Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi. 4 Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na. 5 On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ. 6 On si ranṣẹ pè Baraki ọmọ Abinoamu lati Kedeṣi-naftali jade wá, o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun Israeli kò ha ti paṣẹ pe, Lọ sunmọ òke Tabori, ki o si mú ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ọmọ Naftali, ati ninu awọn ọmọ Sebuluni pẹlu rẹ. 7 Emi o si fà Sisera, olori ogun Jabini, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati ogun rẹ̀, sọdọ rẹ si odò Kiṣoni; emi o si fi i lé ọ lọwọ. 8 Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ. 9 On si wipe, Ni lilọ emi o bá ọ lọ: ṣugbọn ọlá ọ̀na ti iwọ nlọ nì ki yio jẹ́ tirẹ; nitoriti OLUWA yio tà Sisera si ọwọ́ obinrin. Debora si dide, o si bá Baraki lọ si Kedeṣi. 10 Baraki si pè Sebuluni ati Naftali si Kedeṣi; on si lọ pẹlu ẹgba marun ọkunrin lẹhin rẹ̀: Debora si gòke lọ pẹlu rẹ̀. 11 Njẹ Heberi ọmọ Keni, ti yà ara rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọmọ Keni, ani awọn ọmọ Hobabu, ana Mose, o si pa agọ́ rẹ̀ titi dé igi-oaku Saanannimu, ti o wà li àgbegbe Kedeṣi. 12 Nwọn si sọ fun Sisera pe, Baraki ọmọ Abinoamu ti lọ si òke Tabori. 13 Sisera si kó gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ jọ, ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, lati Haroṣeti awọn orilẹ-ède wá si odò Kiṣoni. 14 Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin. 15 OLUWA si fi oju idà ṣẹgun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun rẹ̀, niwaju Baraki; Sisera si sọkalẹ kuro li ori kẹkẹ́ rẹ̀, o si fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ. 16 Ṣugbọn Baraki lepa awọn kẹkẹ́, ati ogun na, titi dé Haroṣeti awọn orilẹ-ède: gbogbo ogun Sisera si ti oju idà ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò si kù. 17 Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni. 18 Jaeli si jade lọ ipade Sisera, o si wi fun u pe, Yà wá, oluwa mi, yà sọdọ mi; má bẹ̀ru. On si yà sọdọ rẹ̀ sinu agọ́, o si fi kubusu bò o. 19 On si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fun mi li omi diẹ mu; nitoriti ongbẹ ngbẹ mi. O si ṣí igo warà kan, o si fi fun u mu, o si bò o lara. 20 On si wi fun u pe, Duro li ẹnu-ọ̀na agọ́, yio si ṣe, bi ẹnikan ba wá, ti o si bi ọ lère pe, ọkunrin kan wà nihin bi? ki iwọ wipe, Kò sí. 21 Nigbana ni Jaeli aya Heberi mú iṣo-agọ́ kan, o si mú õlù li ọwọ́ rẹ̀, o si yọ́ tọ̀ ọ, o si kàn iṣo na mọ́ ẹbati rẹ̀, o si wọ̀ ilẹ ṣinṣin; nitoriti o sùn fọnfọn; bẹ̃ni o daku, o si kú. 22 Si kiyesi i, bi Baraki ti nlepa Sisera, Jaeli wá pade, rẹ̀, o si wi fun u pe, Wá, emi o si fi ọkunrin ti iwọ nwá hàn ọ. O si wá sọdọ rẹ̀; si kiyesi i, Sisera dubulẹ li okú, iṣo-agọ́ na si wà li ẹbati rẹ̀. 23 Bẹ̃li Ọlọrun si tẹ̀ ori Jabini ọba Kenaani ba li ọjọ́ na niwaju awọn ọmọ Israeli. 24 Ọwọ́ awọn ọmọ Israeli si le siwaju ati siwaju si Jabini ọba Kenaani, titi nwọn fi run Jabini ọba Kenaani.

Onidajọ 5

Orin Debora ati Baraki

1 NIGBANA ni Debora on Baraki ọmọ Abinoamu kọrin li ọjọ́ na, wipe, 2 Nitori bi awọn olori ti ṣaju ni Israeli, nitori bi awọn enia ti fi tinutinu wá, ẹ fi ibukún fun OLUWA. 3 Ẹ gbọ́, ẹnyin ọba; ẹ feti nyin silẹ, ẹnyin ọmọ alade; emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyìn si OLUWA, Ọlọrun Israeli. 4 OLUWA, nigbati iwọ jade kuro ni Seiri, nigbati iwọ nyan jade lati pápa Edomu wá, ilẹ mìtiti, awọn ọrun si kánsilẹ, ani awọsanma pẹlu kán omi silẹ. 5 Awọn òke nla yọ́ niwaju OLUWA, ani Sinai yọ́ niwaju OLUWA; Ọlọrun Israeli. 6 Li ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, li ọjọ́ Jaeli, awọn ọ̀na opópo da, awọn èro si nrìn li ọ̀na ìkọ̀kọ̀. 7 Awọn olori tán ni Israeli, nwọn tán, titi emi Debora fi dide, ti emi dide bi iya ni Israeli. 8 Nwọn ti yàn ọlọrun titun; nigbana li ogun wà ni ibode: a ha ri asà tabi ọ̀kọ kan lãrin ẹgba ogún ni Israeli bi? 9 Àiya mi fà si awọn alaṣẹ Israeli, awọn ti nwọn fi tinutinu wá ninu awọn enia: ẹ fi ibukún fun OLUWA. 10 Ẹ sọ ọ, ẹnyin ti ngùn kẹtẹkẹtẹ funfun, ẹnyin ti njoko lori ẹni daradara, ati ẹnyin ti nrìn li ọ̀na. 11 Li ọ̀na jijìn si ariwo awọn tafàtafa nibiti a gbé nfà omi, nibẹ̀ ni nwọn o gbé sọ iṣẹ ododo OLUWA, ani iṣẹ ododo ijọba rẹ̀ ni Israeli. Nigbana ni awọn enia OLUWA sọkalẹ lọ si ibode. 12 Jí, jí, Debora; Jí, jí, kọ orin: dide, Baraki, ki o si ma kó awọn igbekun rẹ ni igbekun, iwọ ọmọ Abinoamu. 13 Nigbana ni iyokù ninu awọn ọlọ̀tọ ati awọn enia sọkalẹ; OLUWA sọkalẹ sori awọn alagbara fun mi. 14 Lati Efraimu ni nwọn ti wá awọn ti gbongbo wọn wà ni Amaleki; lẹhin rẹ, Benjamini, lãrin awọn enia rẹ; lati Makiri ni awọn alaṣẹ ti sọkalẹ wá, ati lati Sebuluni li awọn ẹniti nmú ọ̀pá-oyè lọwọ. 15 Awọn ọmọ-alade Issakari wà pẹlu Debora; bi Issakari ti ri, bẹ̃ni Baraki; nwọn sure li ẹsẹ̀ lọ si afonifoji na. Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà. 16 Ẽṣe ti iwọ fi joko lãrin agbo-agutan lati ma gbọ́ fere oluṣọ-agutan? Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà. 17 Gileadi joko loke odò Jordani: ẽṣe ti Dani fi joko ninu ọkọ̀? Aṣeri joko leti okun, o si ngbé ebute rẹ̀. 18 Sebuluni li awọn enia, ti o fi ẹmi wọn wewu ikú, ati Naftali, ni ibi giga pápa. 19 Awọn ọba wá nwọn jà; nigbana li awọn ọba Kenaani jà ni Taanaki leti odò Megiddo: nwọn kò si gbà ère owo. 20 Nwọn jà lati ọrun wá, awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà. 21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò igbani, odò Kiṣoni. Hã ọkàn mi, ma yan lọ ninu agbara. 22 Nigbana ni patako ẹsẹ̀ ẹṣin kì ilẹ, nitori ire-sisá, iré-sisá awọn alagbara wọn. 23 Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara. 24 Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́. 25 O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye. 26 O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin. 27 Li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu, o dubulẹ: li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu: ni ibi ti o gbè wolẹ, nibẹ̀ na li o ṣubu kú. 28 Iya Sisera nwò oju-ferese, o si kigbe, o kigbe li oju-ferese ọlọnà pe; Ẽṣe ti kẹkẹ́ rẹ̀ fi pẹ bẹ̃ lati dé? Ẽṣe ti ẹsẹ̀ kẹkẹ̀ rẹ̀ fi duro lẹhin? 29 Awọn obinrin rẹ̀ amoye da a lohùn, ani, on si ti da ara rẹ̀ lohùn pe, 30 Nwọn kò ha ti ri, nwọn kò ha ti pín ikogun bi? fun olukuluku ọkunrin wundia kan tabi meji; fun Sisera ikogun-aṣọ alarabara, ikógun-aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ, aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ ni ìha mejeji, li ọrùn awọn ti a kó li ogun. 31 Bẹ̃ni ki o jẹ ki gbogbo awọn ọtá rẹ ki o ṣegbé OLUWA: ṣugbọn jẹ ki awọn ẹniti o fẹ́ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ̀. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún.

Onidajọ 6

Gideoni

1 AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje. 2 Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni. 3 O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá; 4 Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ. 5 Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run. 6 Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA. 7 O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA nitori awọn Midiani, 8 OLUWA si rán wolĩ kan si awọn ọmọ Israeli: ẹniti o wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Emi mú nyin gòke ti Egipti wá, mo si mú nyin jade kuro li oko-ẹrú; 9 Emi si gbà nyin li ọwọ́ awọn ara Egipti, ati li ọwọ́ gbogbo awọn ti npọ́n nyin loju, mo si lé wọn kuro niwaju nyin, mo si fi ilẹ wọn fun nyin; 10 Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́. 11 Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani. 12 Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara. 13 Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ. 14 OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi? 15 O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi. 16 OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan. 17 On si wi fun u pe, Bi o ba ṣepe mo ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, njẹ fi àmi kan hàn mi pe iwọ bá mi sọ̀rọ. 18 Máṣe lọ kuro nihin, emi bẹ̀ ọ, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, ti emi o si fi mú ọrẹ mi fun ọ wá, ati ti emi o si fi gbé e kalẹ niwaju rẹ. On si wipe, Emi o duro titi iwọ o si fi pada wá. 19 Gideoni si wọ̀ inu ilé lọ, o si pèse ọmọ ewurẹ kan, ati àkara alaiwu ti iyẹfun òṣuwọn efa kan: ẹran na li o fi sinu agbọ̀n, omi rẹ̀ li o si fi sinu ìkoko, o si gbé e jade tọ̀ ọ wá labẹ igi-oaku na, o si gbé e siwaju rẹ̀. 20 Angeli Ọlọrun na si wi fun u pe, Mú ẹran na, ati àkara alaiwu na, ki o si fi wọn lé ori okuta yi, ki o si dà omi ẹran na silẹ. On si ṣe bẹ̃. 21 Nigbana ni angeli OLUWA nà ọpá ti o wà li ọwọ rẹ̀, o si fi ori rẹ̀ kàn ẹran na ati àkara alaiwu na; iná si là lati inu okuta na jade, o si jó ẹran na, ati àkara alaiwu; angeli OLUWA na si lọ kuro niwaju rẹ̀. 22 Gideoni si ri pe angeli OLUWA ni; Gideoni si wipe, Mo gbé, OLUWA Ọlọrun! nitoriti emi ri angeli OLUWA li ojukoju. 23 OLUWA si wi fun u pe, Alafia fun ọ; má ṣe bẹ̀ru: iwọ́ ki yio kú. 24 Nigbana ni Gideoni mọ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jehofa-ṣalomu: o wà ni Ofra ti awọn Abiesri sibẹ̀ titi di oni. 25 O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ: 26 Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun. 27 Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru. 28 Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ. 29 Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi. 30 Nigbana li awọn ọkunrin ilu na wi fun Joaṣi pe, Mú ọmọ rẹ jade wá ki o le kú: nitoripe o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ati nitoriti o bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ. 31 Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. 32 Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ. 33 Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli. 34 Ṣugbọn ẹmi OLUWA bà lé Gideoni, on si fun ipè; Abieseri si kójọ sẹhin rẹ̀. 35 On si rán onṣẹ si gbogbo Manasse; awọn si kójọ sẹhin rẹ̀ pẹlu: o si rán onṣẹ si Aṣeri, ati si Sebuluni, ati si Naftali; nwọn si gòke wá lati pade wọn. 36 Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Bi iwọ o ba ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, bi iwọ ti wi, 37 Kiyesi i, emi o fi irun agutan le ilẹ-pakà; bi o ba ṣepe ìri sẹ̀ sara kìki irun nikan, ti gbogbo ilẹ si gbẹ, nigbana li emi o mọ̀ pe iwọ o ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, gẹgẹ bi iwọ ti wi. 38 Bẹ̃li o si ri: nitoriti on dide ni kùtukutu ijọ́ keji, o si fọ́n irun agutan na, o si fọ́n ìri na kuro lara rẹ̀, ọpọ́n kan si kún fun omi. 39 Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Má ṣe jẹ ki ibinu rẹ ki o rú si mi, emi o sọ̀rọ lẹ̃kanṣoṣo yi: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o fi irun na ṣe idanwò lẹ̃kan yi; jẹ ki irun agutan nikan ki o gbẹ, ṣugbọn ki ìri ki o wà lori gbogbo ilẹ. 40 Ọlọrun si ṣe bẹ̃ li oru na: nitoriti irun agutan na gbẹ, ìri si wà lori gbogbo ilẹ na.

Onidajọ 7

1 NIGBANA ni Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, dide ni kùtukutu, nwọn si dó lẹba orisun Harodu: ibudó Midiani si wà ni ìha ariwa wọn, nibi òke More, li afonifoji. 2 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là. 3 Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun. 4 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ. 5 Bẹ̃li o mú awọn enia na wá si odò: OLUWA si wi fun Gideoni pe, Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ̀ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ̀; bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ lati mu omi. 6 Iye awọn ẹniti o lá omi, ti nwọn fi ọwọ́ wọn si ẹnu wọn, jẹ́ ọdunrun ọkunrin: ṣugbọn gbogbo awọn enia iyokù kunlẹ li ẽkun wọn lati mu omi. 7 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Nipaṣe ọdunrun ọkunrin wọnyi ti o lá omi li emi o gbà nyin, emi o si fi awọn Midiani lé ọ lọwọ: jẹ ki gbogbo awọn iyokù lọ olukuluku si ipò rẹ̀. 8 Awọn enia na si mu onjẹ ati ipè li ọwọ́ wọn: on si rán gbogbo Israeli lọ, olukuluku sinu agọ́ rẹ̀, o si da ọdunrun ọkunrin nì duro: ibudó Midiani si wà nisalẹ rẹ̀ li afonifoji. 9 O si ṣe li oru na, ni OLUWA wi fun u pe, Dide, sọkalẹ lọ si ibudó; nitoriti mo ti fi i lé ọ lọwọ. 10 Ṣugbọn bi iwọ ba mbẹ̀ru lati sọkalẹ lọ, ki iwọ ati Pura iranṣẹ rẹ sọkalẹ lọ si ibudo: 11 Iwọ o si gbọ́ ohun ti nwọn nwi; lẹhin eyi ni ọwọ́ rẹ yio lí agbara lati sọkalẹ lọ si ibudó. Nigbana ni ti on ti Pura iranṣẹ rẹ̀ sọkalẹ lọ si ìha opin awọn ti o hamora, ti o wà ni ibudó. 12 Awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati gbogbo awọn ọmọ ìha ìla-õrùn tò lọ titi li afonifoji gẹgẹ bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; ibakasiẹ wọn kò si ní iye, bi iyanrin ti mbẹ leti okun li ọ̀pọlọpọ. 13 Nigbati Gideoni si dé, kiyesi i, ọkunrin kan nrọ́ alá fun ẹnikeji rẹ̀, o si wipe, Kiyesi i, emi lá alá kan, si wò o, àkara ọkà-barle kan ṣubu si ibudó Midiani, o si bọ́ sinu agọ́ kan, o si kọlù u tobẹ̃ ti o fi ṣubu, o si doju rẹ̀ de, agọ́ na si ṣubu. 14 Ekeji rẹ̀ si da a lohùn, wipe, Eyiyi ki iṣe ohun miran bikoṣe idà Gideoni ọmọ Joaṣi, ọkunrin kan ni Israeli: nitoripe Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ibudo lé e lọwọ. 15 O si ṣe, nigbati Gideoni gbọ́ rirọ́ alá na, ati itumọ̀ rẹ̀, o tẹriba; o si pada si ibudó Israeli, o si wipe, Ẹ dide; nitoriti OLUWA ti fi ogun Midiani lé nyin lọwọ. 16 On si pín ọdunrun ọkunrin na si ẹgbẹ mẹta, o si fi ipè lé olukuluku wọn lọwọ, pẹlu ìṣa ofo, òtufu si wà ninu awọn ìṣa na. 17 On si wi fun wọn pe, Ẹ wò mi, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ: si kiyesi i, nigbati mo ba dé opin ibudó na, yio si ṣe bi emi ba ti ṣe, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe. 18 Nigbati mo ba fun ìpe, emi ati gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi, nigbana ni ki ẹnyin pẹlu ki o fun ìpe yiká gbogbo ibudó na, ki ẹnyin ki o si wi pe, Fun OLUWA, ati fun Gideoni. 19 Bẹ̃ni Gideoni, ati ọgọrun ọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀, wá si opin ibudó, ni ibẹ̀rẹ iṣọ́ ãrin, nigbati nwọn ṣẹṣẹ yàn iṣọ́ sode: nwọn fun ipè, nwọn si fọ́ ìṣa ti o wà li ọwọ́ wọn. 20 Ẹgbẹ mẹtẹta na si fun ipè wọn, nwọn si fọ́ ìṣa wọn, nwọn si mú awọn òtufu li ọwọ́ òsi wọn, ati ipè li ọwọ́ ọtún lati fun: nwọn si kigbe li ohùn rara pe, Idà OLUWA, ati ti Gideoni. 21 Olukuluku ọkunrin si duro ni ipò rẹ̀ yi ibudó na ká: gbogbo ogun na si sure, nwọn si kigbe, nwọn si sá. 22 Awọn ọkunrin na fun ọdunrun ipè, OLUWA si yí idà olukuluku si ẹnikeji rẹ̀, ati si gbogbo ogun na: ogun na si sá titi dé Beti-ṣita ni ìha Serera, dé àgbegbe Abeli-mehola, leti Tabati. 23 Awọn ọkunrin Israeli si kó ara wọn jọ lati Naftali, ati lati Aṣeri ati lati gbogbo Manasse wá, nwọn si lepa awọn Midiani. 24 Gideoni si rán onṣẹ lọ si gbogbo òke Efraimu, wipe, Ẹ sọkalẹ wá pade awọn Midiani, ki ẹ si tète gbà omi wọnni dé Beti-bara ani Jordani. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin Efraimu kó ara wọn jọ, nwọn si gbà omi wọnni, titi dé Beti-bara ani Jordani. 25 Nwọn si mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani, Orebu ati Seebu; Orebu ni nwọn si pa lori apata Orebu, ati Seebu ni nwọn si pa ni ibi-ifọnti Seebu, nwọn si lepa awọn ara Midiani, nwọn si mú ori Orebu ati Seebu wá fi fun Gideoni li apa keji odò Jordani.

Onidajọ 8

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani ní Àṣẹ́tán

1 AWỌN ọkunrin Efraimu si wi fun u pe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa bayi, ti iwọ kò fi pè wa, nigbati iwọ nlọ bá awọn ara Midiani jà? Nwọn si bá a sọ̀ gidigidi. 2 On si wi fun wọn pe, Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin? Ẽṣẹ́ àjara Efraimu kò ha san jù ikore-àjara Abieseri lọ? 3 Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì. 4 Gideoni si dé odò Jordani, o si rekọja, on ati ọdunrun ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀, o di ãrẹ, ṣugbọn nwọn nlepa sibẹ̀. 5 On si wi fun awọn ọkunrin Sukkotu pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ìṣu-àkara melokan fun awọn enia wọnyi ti ntọ̀ mi lẹhin: nitoriti o di ãrẹ fun wọn, emi si nlepa Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani. 6 Awọn ọmọ-alade Sukkotu si wi pe, ọwọ́ rẹ ha ti ítẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ? 7 Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin. 8 On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn. 9 On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀. 10 Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu. 11 Gideoni si gbà ọ̀na awọn ti ngbé inú agọ́ ni ìha ìla-õrùn Noba ati Jogbeha gòke lọ, o si kọlù ogun na; nitoriti ogun na ti sọranù. 12 Seba ati Salmunna si sá; on si lepa wọn; o si mù awọn ọba Midiani mejeji na, Seba ati Salmunna, o si damu gbogbo ogun na. 13 Gideoni ọmọ Joaṣi si pada lẹhin ogun na, ni ibi ati gòke Heresi. 14 O si mú ọmọkunrin kan ninu awọn ọkunrin Sukkotu, o si bère lọwọ rẹ̀: on si ṣe apẹrẹ awọn ọmọ-alade Sukkotu fun u, ati awọn àgba ti o wà nibẹ̀, mẹtadilọgọrin ọkunrin. 15 On si tọ̀ awọn ọkunrin Sukkotu na wá, o si wi fun wọn pe, Wò Seba ati Salmunna, nitori awọn ẹniti ẹnyin fi gàn mi pe, Ọwọ́ rẹ ha ti tẹ Seba ati Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ọkunrin rẹ ti ãrẹ mu li onjẹ? 16 On si mú awọn àgbagba ilu na, ati ẹgún ijù ati oṣuṣu, o si fi kọ́ awọn ọkunrin Sukkotu li ọgbọ́n. 17 On si wó ile-ẹṣọ́ Penueli, o si pa awọn ọkunrin ilu na. 18 Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba. 19 On si wipe, Arakunrin mi ni nwọn, ọmọ iya mi ni nwọn iṣe: bi OLUWA ti wà, ibaṣepe ẹnyin da wọn si, emi kì ba ti pa nyin. 20 On si wi fun Jeteri arẹmọ rẹ̀ pe, Dide, ki o si pa wọn. Ṣugbọn ọmọkunrin na kò fà idà rẹ̀ yọ: nitori ẹ̀ru bà a, nitoripe ọmọde ni iṣe. 21 Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn. 22 Nigbana li awọn ọkunrin Israeli wi fun Gideoni pe, Iwọ ma ṣe olori wa, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ pẹlu: nitoripe o gbà wa lọwọ awọn ara Midiani. 23 Gideoni si wi fun wọn pe, Emi ki yio ṣe olori nyin, bẹ̃ni ọmọ mi ki yio ṣe olori nyin: OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin. 24 Gideoni si wi fun wọn pe, Emi o bère nkan lọwọ nyin, pe ki olukuluku nyin ki o le fi oruka-etí ti mbẹ ninu ikogun rẹ̀ fun mi. (Nitoriti nwọn ní oruka-etí ti wurà, nitoripe ọmọ Iṣmaeli ni nwọn iṣe.) 25 Nwọn si dahùn wipe, Tinutinu li awa o fi mú wọn wá. Nwọn si tẹ́ aṣọ kan, olukuluku nwọn si sọ oruka-etí ikogun rẹ̀ si i. 26 Ìwọn oruka-etí wurà na ti o bère lọwọ wọn jẹ́ ẹdẹgbẹsan ṣekeli wurà: làika ohun ọṣọ́ wọnni, ati ohun sisorọ̀, ati aṣọ elesè-àluko ti o wà lara awọn ọba Midiani, ati li àika ẹ̀wọn ti o wà li ọrùn ibakasiẹ wọn. 27 Gideoni si fi i ṣe ẹ̀wu-efodu kan, o si fi i si ilu rẹ̀, ni Ofra: gbogbo Israeli si ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin nibẹ̀: o si wa di idẹkun fun Gideoni, ati fun ile rẹ̀. 28 Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni.

Ikú Gideoni

29 Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀. 30 Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀. 31 Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki. 32 Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri. 33 O si ṣe, lojukanna ti Gideoni kú, li awọn ọmọ Israeli pada, nwọn si ṣe panṣaga tọ̀ Baalimu lọ, nwọn si fi Baaliberiti ṣe oriṣa wọn. 34 Awọn ọmọ Israeli kò si ranti OLUWA Ọlọrun wọn, ẹniti o gbà wọn lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn ni ìha gbogbo: 35 Bẹ̃ni nwọn kò si ṣe ore fun ile Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti ṣe fun Israeli.

Onidajọ 9

Abimeleki

1 ABIMELEKI ọmọ Jerubbaali si lọ si Ṣekemu sọdọ awọn arakunrin iya rẹ̀, o si bá wọn sọ̀rọ, ati gbogbo idile ile baba iya rẹ̀, wipe, 2 Emi bẹ̀ nyin, ẹ sọ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu pe, Ẽwo li o rọ̀run fun nyin, ki gbogbo awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, ki o ṣe olori nyin, tabi ki ẹnikan ki o ṣe olori nyin? ki ẹnyin ki o ranti pẹlu pe, emi li egungun nyin, ati ẹran ara nyin. 3 Awọn arakunrin iya rẹ̀ si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi nitori rẹ̀ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu: àiya wọn si tẹ̀ si ti Abimeleki; nitori nwọn wipe, Arakunrin wa ni iṣe. 4 Nwọn si fun u li ãdọrin owo fadakà lati inu ile Baali-beriti wá, Abimeleki si fi i bẹ̀ awọn enia lasan ati alainilari li ọ̀wẹ, nwọn si ntẹ̀le e. 5 On si lọ si ile baba rẹ̀ ni Ofra, o si pa awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, lori okuta kan: ṣugbọn o kù Jotamu abikẹhin ọmọ Jerubbaali; nitoriti o sapamọ́. 6 Gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu si kó ara wọn jọ, ati gbogbo awọn ara ile Millo, nwọn lọ nwọn si fi Abimeleki jẹ́ ọba, ni ibi igi-oaku ile-ẹṣọ́ ti mbẹ ni Ṣekemu. 7 Nigbati nwọn si sọ fun Jotamu, on si lọ o si duro lori òke Gerisimu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o kigbe, o si wi fun wọn pe, Ẹ fetisi ti emi, ẹnyin ọkunrin Ṣekemu, ki Ọlọrun ki o le fetisi ti nyin. 8 Awọn igi lọ li akokò kan ki nwọn ki o le fi ọba jẹ́ lori wọn; nwọn si wi fun igi olifi pe, Wá jọba lori wa. 9 Ṣugbọn igi olifi wi fun wọn pe, Emi ha le fi ọrá mi silẹ, nipa eyiti nwọn nfi mi bù ọlá fun Ọlọrun ati enia, ki emi ki o si wá ṣe olori igi? 10 Awọn igi si wi fun igi ọpọtọ́ pe, Iwọ wá jọba lori wa. 11 Ṣugbọn igi ọpọtọ́ wi fun wọn pe, Emi le fi adùn mi silẹ, ati eso mi daradara, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi? 12 Awọn igi si wi fun àjara pe, Iwọ wá jọba lori wa. 13 Àjara si wi fun wọn pe, Ki emi ki o fi ọti-waini mi silẹ, eyiti nmu inu Ọlọrun ati enia dùn, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi? 14 Nigbana ni gbogbo igi si wi fun igi-ẹgún pe, Iwọ wá jọba lori wa. 15 Igi-ẹgún si wi fun awọn igi pe, Bi o ba ṣepe nitõtọ li ẹnyin fi emi jẹ́ ọba lori nyin, njẹ ẹ wá sá si abẹ ojiji mi: bi kò ba si ṣe bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti inu igi-ẹgún jade wá, ki o si jó awọn igi-kedari ti Lebanoni run. 16 Njẹ nitorina, bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé, ni ti ẹnyin fi Abimeleki jẹ ọba, ati bi ẹnyin ba si ṣe rere si Jerubbaali ati si ile rẹ̀, ti ẹnyin si ṣe si i gẹgẹ bi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀; 17 (Nitoriti baba mi jà fun nyin, o si fi ẹmi rẹ̀ wewu, o si gbà nyin kuro li ọwọ Midiani: 18 Ẹnyin si dide si ile baba mi li oni, ẹnyin si pa awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ãdọrin enia, lori okuta kan, ẹnyin si fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jẹ́ ọba lori awọn Ṣekemu, nitoriti arakunrin nyin ni iṣe;) 19 Njẹ bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé si Jerubbaali ati si ile rẹ̀ li oni yi, njẹ ki ẹnyin ki o ma yọ̀ si Abimeleki, ki on pẹlu si ma yọ̀ si nyin: 20 Ṣugbọn bi kò ba si ri bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti ọdọ Abimeleki jade wá, ki o si jó awọn ọkunrin Ṣekemu run, ati ile Millò: jẹ ki iná ki o si ti ọdọ awọn ọkunrin Ṣekemu ati ile Millo jade wá, ki o si jó Abimeleki run. 21 Jotamu si ṣí, o sálọ, o si lọ si Beeri, o si joko sibẹ̀, nitori ìbẹru Abimeleki arakunrin rẹ̀. 22 Abimeleki sí ṣe olori awọn ọmọ Israeli li ọdún mẹta. 23 Ọlọrun si rán ẹmi buburu sãrin Abimeleki ati awọn ọkunrin Ṣekemu; awọn ọkunrin Ṣekemu si fi arekereke bá Abimeleki lò: 24 Ki ìwa-ìka ti a ti hù si awọn ãdọrin ọmọ Jerubbaali ki o le wá, ati ẹ̀jẹ wọn sori Abimeleki arakunrin wọn, ẹniti o pa wọn; ati sori awọn ọkunrin Ṣekemu, awọn ẹniti o ràn a lọwọ lati pa awọn arakunrin rẹ̀. 25 Awọn ọkunrin Ṣekemu si yàn awọn enia ti o ba dè e lori òke, gbogbo awọn ti nkọja lọdọ wọn ni nwọn si njà a li ole: nwọn si sọ fun Abimeleki. 26 Gaali ọmọ Ebedi si wá ti on ti awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si kọja lọ si Ṣekemu: awọn ọkunrin Ṣekemu si gbẹkẹ wọn le e. 27 Nwọn si jade lọ si oko, nwọn si ká eso-àjara wọn, nwọn si fọ́n eso na, nwọn si nṣe ariya, nwọn si lọ si ile oriṣa wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu, nwọn si fi Abimeleki ré. 28 Gaali ọmọ Ebedi si wipe, Tani Abimeleki? ta si ni Ṣekemu, ti awa o fi ma sìn i? Ṣe ọmọ Jerubbaali ni iṣe? ati Sebulu ijoye rẹ̀? ẹ mã sìn awọn ọkunrin Hamoru baba Ṣekemu: ṣugbọn nitori kili awa o ha ṣe ma sìn on? 29 Awọn enia wọnyi iba wà ni ikawọ mi! nigbana ni emi iba ṣí Abimeleki ni ipò. On si wi fun Abimeleki pe, Gbá ogun kún ogun rẹ, ki o si jade. 30 Nigbati Sebulu alaṣẹ ilu na si gbọ́ ọ̀rọ Gaali ọmọ Ebedi, o binu gidigidi. 31 On si rán awọn onṣẹ ìkọkọ si Abimeleki, wipe, Kiyesi i, Gaali ọmọ Ebedi ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si Ṣekemu; si kiyesi i, nwọn rú ilú na sokè si ọ. 32 Njẹ nitorina, dide li oru, iwọ ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ, ki ẹnyin ki o si ba sinu oko: 33 Yio si ṣe, li owurọ̀, lojukanna bi õrùn ba si ti là, ki iwọ ki o dide ni kùtukutu owurọ̀, ki iwọ ki o si kọlù ilu na: si kiyesi i, nigbati on ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ ba jade tọ̀ ọ, nigbana ni ki iwọ ki o ṣe si wọn bi iwọ ba ti ri pe o yẹ. 34 Abimeleki si dide, ati gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ li oru, nwọn si ba ni ipa mẹrin leti Ṣekemu. 35 Gaali ọmọ Ebedi si jade, o si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: Abimeleki si dide, ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, kuro ni ibùba. 36 Nigbati Gaali si ri awọn enia na, o wi fun Sebulu pe, Wò o, awọn enia nti ori òke sọkalẹ wa. Sebulu si wi fun u pe, Ojiji òke wọnni ni iwọ ri bi ẹnipe enia. 37 Gaali si tun wipe, Wò o, awọn enia nti òke sọkalẹ li agbedemeji ilẹ wá, ẹgbẹ kan si nti ọ̀na igi-oaku Meonenimu wá. 38 Nigbana ni Sebulu wi fun u pe, Nibo li ẹnu rẹ wà nisisiyi, ti iwọ fi wipe, Tani Abimeleki, ti awa o fi ma sìn i? awọn enia ti iwọ ti gàn kọ́ ni iwọnyi? jọwọ jade lọ, nisisiyi, ki o si bà wọn jà. 39 Gaali si jade niwaju awọn ọkunrin Ṣekemu, o si bá Abimeleki jà. 40 Abimeleki si lé e, on si sá niwaju rẹ̀, ọ̀pọlọpọ ninu nwọn ti o gbọgbẹ si ṣubu, titi dé ẹnu-ọ̀na ibode. 41 Abimeleki si joko ni Aruma: Sebulu si tì Gaali ati awọn arakunrin rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe joko ni Ṣekemu. 42 O si ṣe ni ijọ keji, ti awọn enia si jade lọ sinu oko; nwọn si sọ fun Abimeleki. 43 On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn. 44 Abimeleki, ati ẹgbẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀ sure siwaju, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: ẹgbẹ meji si sure si gbogbo awọn enia na ti o wà ninu oko, nwọn si kọlù wọn. 45 Abimeleki si bá ilu na jà ni gbogbo ọjọ́ na; on si kó ilu na, o si pa awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, o si wó ilu na palẹ, o si fọn iyọ̀ si i. 46 Nigbati gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu gbọ́, nwọn si wọ̀ inu ile-ẹṣọ́ oriṣa Eliberiti lọ. 47 A si sọ fun Abimeleki pe, gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀. 48 Abimeleki si gùn ori òke Salmoni lọ, on ati gbogbo enia ti o wà pẹlu rẹ̀; Abimeleki si mu ãke kan li ọwọ́ rẹ̀, o si ke ẹka kan kuro lara igi, o si mú u, o si gbé e lé èjika rẹ̀, o si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Ohun ti ẹnyin ri ti emi ṣe, ẹ yára, ki ẹ si ṣe bi emi ti ṣe. 49 Gbogbo awọn enia na pẹlu, olukuluku si ke ẹka tirẹ̀, nwọn si ntọ̀ Abimeleki lẹhin, nwọn si fi wọn sinu ile-ẹṣọ́ na, nwọn si tinabọ ile na mọ́ wọn lori, tobẹ̃ ti gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹlu, ìwọn ẹgbẹrun enia, ọkunrin ati obinrin. 50 Nigbana ni Abimeleki lọ si Tebesi, o si dótì Tebesi, o si kó o. 51 Ṣugbọn ile-ẹṣọ́ ti o lagbara wà ninu ilu na, nibẹ̀ ni gbogbo awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati gbogbo awọn ẹniti o wà ni ilu na gbé sá si, nwọn si fara wọn mọ́ ibẹ̀; nwọn si gòke ile-ẹṣọ́ na lọ. 52 Abimeleki si wá si ibi ile-ẹṣọ́ na, o si bá a jà, o si sunmọ ẹnu-ọ̀na ile-ẹṣọ na lati fi iná si i. 53 Obinrin kan si sọ ọlọ lù Abimeleki li ori, o si fọ́ ọ li agbári. 54 Nigbana li o pè ọmọkunrin ti nrù ihamọra rẹ̀ kánkan, o si wi fun u pe, Fà idà rẹ yọ, ki o si pa mi, ki awọn enia ki o má ba wi nipa ti emi pe, Obinrin li o pa a. Ọmọkunrin rẹ̀ si gún u, bẹ̃li o si kú. 55 Nigbati awọn ọkunrin Israeli si ri pe, Abimeleki kú, nwọn si lọ olukuluku si ipò rẹ̀. 56 Bayi li Ọlọrun san ìwa buburu Abimeleki, ti o ti hù si baba rẹ̀, niti pe, o pa ãdọrin awọn arakunrin rẹ̀: 57 Ati gbogbo ìwa buburu awọn ọkunrin Ṣekemu li Ọlọrun si múpada sori wọn: egún Jotamu ọmọ Jerubbaali si ṣẹ sori wọn.

Onidajọ 10

Tola

1 LẸHIN Abimeleki li ẹnikan si dide lati gbà Israeli là, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, ọkunrin Issakari kan; o si ngbé Ṣamiri li òke Efraimu. 2 On si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹtalelogun o si kú, a si sin i ni Ṣamiri.

Jairi

3 Lẹhin rẹ̀ ni Jairi dide, ara Gileadi; o si ṣe idajọ Israeli li ọdún mejilelogun. 4 On si ní ọgbọ̀n ọmọkunrin ti ngùn ọgbọ̀n ọmọ kẹtẹkẹtẹ, nwọn si ní ọgbọ̀n ilu ti a npè ni Haffoti-jairi titi o fi di oni, eyiti o wà ni ilẹ Gileadi. 5 Jairi si kú, a si sin i ni Kamoni.

Jẹfuta

6 Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu, ati Aṣtarotu, ati awọn oriṣa Siria, ati awọn oriṣa Sidoni, ati awọn oriṣa Moabu, ati awọn oriṣa awọn ọmọ Ammoni, ati awọn oriṣa awọn Filistini; nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn kò si sìn i. 7 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni. 8 Li ọdún na nwọn ni awọn ọmọ Israeli lara, nwọn si pọ́n wọn loju: ọdún mejidilogun ni nwọn fi ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ti o wà ni ìha keji Jordani ni ilẹ awọn Amori, ti o wà ni Gileadi, lara. 9 Awọn ọmọ Ammoni si gòke odò Jordani lati bá Juda jà pẹlu, ati Benjamini, ati ile Efraimu; a si ni Israeli lara gidigidi. 10 Awọn ọmọ Israeli si kepè OLUWA wipe, Awa ti ṣẹ̀ si ọ, nitoriti awa ti kọ̀ Ọlọrun wa silẹ, a si nsín Baalimu. 11 OLUWA si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi kò ti gbà nyin kuro lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ awọn ọmọ Amori, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini? 12 Awọn ara Sidoni pẹlu, ati awọn Amaleki, ati awọn Maoni si ti npọ́n nyin loju; ẹnyin kepè mi, emi si gbà nyin lọwọ wọn. 13 Ṣugbọn ẹnyin kọ̀ mi silẹ, ẹ si nsìn ọlọrun miran: nitorina emi ki yio tun gbà nyin mọ́. 14 Ẹ lọ kigbepè awọn oriṣa ti ẹnyin ti yàn; jẹ ki nwọn ki o gbà nyin li akokò wahalà nyin. 15 Awọn ọmọ Israeli si wi fun OLUWA pe, Awa ti ṣẹ̀: ohunkohun ti o ba tọ́ li oju rẹ ni ki o fi wa ṣe; sá gbà wa li oni yi, awa bẹ̀ ọ. 16 Nwọn si kó ajeji ọlọrun wọnni ti o wà lọdọ wọn kuro, nwọn si nsìn OLUWA: ọkàn rẹ̀ kò si gbà òṣi Israeli mọ́. 17 Nigbana ni awọn ọmọ Ammoni kó ara wọn jọ nwọn si dó si Gileadi. Awọn ọmọ Israeli si kó ara wọn jọ, nwọn si dó si Mispa. 18 Awọn enia na, awọn olori Gileadi si wi fun ara wọn pe, ọkunrin wo ni yio bẹ̀rẹsi bá awọn ọmọ Ammoni jà? on na ni yio ṣe olori gbogbo awọn ara Gileadi.

Onidajọ 11

1 JEFTA ara Gileadi si jẹ́ akọni ọkunrin, on si jẹ́ ọmọ panṣaga obinrin kan: Gileadi si bi Jefta. 2 Aya Gileadi si bi awọn ọmọkunrin fun u; nigbati awọn ọmọ aya na si dàgba, nwọn si lé Jefta jade, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ki yio jogún ni ile baba wa; nitoripe ọmọ ajeji obinrin ni iwọ iṣe. 3 Nigbana ni Jefta sá kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, on si joko ni ile Tobu: awọn enia lasan si kó ara wọn jọ sọdọ Jefta, nwọn si bá a jade lọ, 4 O si ṣe lẹhin ijọ́ melokan, awọn ọmọ Ammoni bá Israeli jagun. 5 O si ṣe nigbati awọn Ammoni bá Israeli jagun, awọn àgba Gileadi si lọ mú Jefta lati ilẹ Tobu wa. 6 Nwọn si wi fun Jefta pe, Wá, jẹ́ olori wa, ki awa ki o le bá awọn ọmọ Ammoni jà. 7 Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Ẹnyin kò ha ti korira mi, ẹnyin kò ha ti lé mi kuro ni ile baba mi? ẽ si ti ṣe ti ẹnyin fi tọ̀ mi wá nisisiyi nigbati ẹnyin wà ninu ipọnju? 8 Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Nitorina li awa ṣe pada tọ̀ ọ nisisiyi, ki iwọ ki o le bá wa lọ, ki o si bá awọn ọmọ Ammoni jà, ki o si jẹ́ olori wa ati ti gbogbo awọn ara Gileadi. 9 Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Bi ẹnyin ba mú mi pada lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti OLUWA ba si fi wọn fun mi, emi o ha jẹ́ olori nyin bi? 10 Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Jẹ ki OLUWA ki o ṣe ẹlẹri lãrin wa, lõtọ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ bẹ̃li awa o ṣe. 11 Nigbana ni Jefta bá awọn àgba Gileadi lọ, awọn enia na si fi i jẹ́ olori ati balogun wọn: Jefta si sọ gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ niwaju OLUWA ni Mispa. 12 Jefta si rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni, wipe, Kili o ṣe temi tirẹ, ti iwọ fi tọ̀ mi wá, lati jà ni ilẹ mi? 13 Ọba awọn ọmọ Ammoni si da awọn onṣẹ Jefta lohùn pe, Nitoriti Israeli ti gbà ilẹ mi, nigbati nwọn gòke ti Egipti wá, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati titi dé Jordani: njẹ́ nisisiyi fi ilẹ wọnni silẹ li alafia. 14 Jefta si tun rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni: 15 O si wi fun u pe, Bayi ni Jefta wi, Israeli kò gbà ilẹ Moabu, tabi ilẹ awọn ọmọ Ammoni: 16 Ṣugbọn nigbati Israeli gòke ti Egipti wá, ti nwọn si nrìn li aginjù, titi dé Okun Pupa, ti nwọn si dé Kadeṣi; 17 Nigbana ni Israeli rán onṣẹ si ọba Edomu, wipe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja ni ilẹ rẹ: ṣugbọn ọba Edomu kò gbọ́. Bẹ̃ gẹgẹ o si ranṣẹ si ọba Moabu pẹlu: ṣugbọn kò fẹ́: Israeli si joko ni Kadeṣi. 18 Nigbana ni o rìn lãrin aginjù o si yi ilẹ Edomu, ati ilẹ Moabu ká, o si yọ ni ìha ìla-õrùn ilẹ Moabu, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ṣugbọn nwọn kò wá sinu àla Moabu, nitoripe Arnoni ni àla Moabu. 19 Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn Amori, ọba Heṣboni; Israeli si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o kọja lãrin ilẹ rẹ si ipò mi. 20 Ṣugbọn Sihoni kò gbẹkẹle Israeli lati kọja li àgbegbe rẹ̀: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo enia rẹ̀ jọ, nwọn si dó ni Jahasi, nwọn si bá Israeli jagun. 21 OLUWA, Ọlọrun Israeli, si fi Sihoni, ati gbogbo enia rẹ̀ lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn: Israeli si gbà gbogbo ilẹ awọn Amori, awọn enia ilẹ na. 22 Nwọn si gbà gbogbo àgbegbe awọn Amori, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati lati aginjù titi dé Jordani. 23 Njẹ bẹ̃ni OLUWA, Ọlọrun Israeli, lé awọn Amori kuro niwaju Israeli awọn enia rẹ̀, iwọ o ha gbà a bi? 24 Iwọ ki yio ha gbà eyiti Kemoṣu oriṣa rẹ fi fun ọ lati ní? Bẹ̃li ẹnikẹni ti OLUWA Ọlọrun wa ba lé kuro niwaju wa, ilẹ wọn ni awa o gbà. 25 Njẹ iwọ ha san jù Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu? on ha bá Israeli ṣe gbolohùn asọ̀ rí, tabi o ha bá wọn jà rí? 26 Nigbati Israeli fi joko ni Heṣboni ati awọn ilu rẹ̀, ati ni Aroeri ati awọn ilu rẹ̀, ati ni gbogbo awọn ilu ti o wà lọ titi de ẹba Arnoni, li ọdunrun ọdún; ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a li akokò na? 27 Nitorina emi kò ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ li o ṣẹ̀ mi ni bibá mi jà: ki OLUWA, Onidajọ, ki o ṣe idajọ li oni lãrin awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Ammoni. 28 Ṣugbọn ọba awọn ọmọ Ammoni kò fetisi ọ̀rọ Jefta, ti o rán si i. 29 Nigbana li ẹmi OLUWA bà lé Jefta, on si kọja Gileadi ati Manasse, o si kọja Mispa ti Gileadi, ati lati Mispa ti Gileadi o si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni. 30 Jefta si jẹ́ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, o si wi pe, Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ, 31 Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun. 32 Jefta si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni, lati bá wọn jà; OLUWA si fi nwọn lé e lọwọ. 33 On si pa wọn ni ipakupa lati Aroeri lọ, titi dé atiwọ̀ Miniti, ani ogún ilu, titi o fi dé Abeli-kiramimu. Bẹ̃li a ṣẹgun awọn ọmọ Ammoni niwaju awọn ọmọ Israeli. 34 Jefta si bọ̀ si ile rẹ̀ ni Mispa, si kiyesi i, ọmọbinrin rẹ̀ si jade wá ipade rẹ̀ ti on ti timbrili ati ijó: on nikan si li ọmọ rẹ̀; lẹhin rẹ̀ kò ní ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. 35 O si ṣe nigbati o ri i, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Yẽ, ọmọ mi! iwọ rẹ̀ mi silẹ gidigidi, iwọ si li ọkan ninu awọn ti nyọ mi lẹnu: nitori emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada. 36 On si wi fun u pe, Baba mi, iwọ ti yà ẹnu rẹ si OLUWA; ṣe si mi gẹgẹ bi eyiti o ti ẹnu rẹ jade; niwọnbi OLUWA ti gbẹsan fun ọ lara awọn ọtá rẹ, ani lara awọn ọmọ Ammoni. 37 On si wi fun baba rẹ̀ pe, Jẹ ki a ṣe nkan yi fun mi: jọwọ mi jẹ li oṣù meji, ki emi ki o lọ ki emi si sọkalẹ sori òke, ki emi ki o le sọkun nitori ìwa-wundia mi, emi ati awọn ẹgbẹ mi. 38 On si wipe, Lọ. O si rán a lọ niwọn oṣù meji: o si lọ, ati on ati awọn ẹgbẹ rẹ̀, o si sọkun nitori ìwa-wundia rẹ̀ lori òke wọnni. 39 O si ṣe li opin oṣù keji, o si pada wá sọdọ baba rẹ̀, ẹniti o ṣe si i gẹgẹ bi ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́: on kò si mọ̀ ọkunrin. O si di ìlana ni Israeli pe, 40 Ki awọn ọmọbinrin Israeli ma lọ li ọdọdún lati pohunrere ọmọbinrin Jefta ara Gileadi li ọjọ́ mẹrin li ọdún.

Onidajọ 12

Jẹfuta ati Àwọn Ará Efuraimu

1 AWỌN ọkunrin Efraimu si kó ara wọn jọ, nwọn si kọja si ìha ariwa; nwọn si wi fun Jefta pe, Ẽṣe ti iwọ fi rekọja lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti iwọ kò si pè wa ki awa ki o le bá ọ lọ? awa o fi iná kun ile rẹ mọ́ ọ lori. 2 Jefta si wi fun wọn pe, Emi ati awọn enia mi ti mbá awọn ọmọ Ammoni jà gidigidi; nigbati emi kepè nyin, ẹnyin kò si gbà mi li ọwọ́ wọn. 3 Nigbati emi si ri pe ẹnyin kò gbà mi, mo fi ẹmi mi wewu, emi si rekọja sọdọ awọn ọmọ Ammoni, OLUWA si fi nwọn lé mi li ọwọ́: nitori kini ẹnyin ha ṣe gòke tọ̀ mi wá li oni, lati bá mi jà? 4 Nigbana ni Jefta kó gbogbo awọn ọkunrin Gileadi jọ, o si bá Efraimu jà: awọn ọkunrin Gileadi si kọlù Efraimu, nitoriti nwọn wipe, Isansa Efraimu li ẹnyin ara Gileadi iṣe, lãrin Efraimu, ati lãrin Manasse, 5 Awọn ara Gileadi si gbà iwọdo Jordani ṣiwaju Efraimu: o si ṣe, nigbati awọn isansa Efraimu ba wipe, Jẹ ki emi ki o rekọja, awọn ọkunrin Gileadi a si wi fun u pe, Efraimu ki iwọ iṣe? Bi on ba si wipe, Rárá o! 6 Nwọn a si wi fun u pe, Njẹ wi pe Ṣibboleti; on si wi pe Sibboleti, nitoripe on kò le pè e rere; nwọn a si mú u, nwọn a si pa a si iwọdo Jordani: awọn ti o si ṣubu li akokò na ninu awọn Efraimu jẹ́ ẹgbã mọkanlelogun enia. 7 Jefta si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹfa. Jefta ara Gileadi si kú, a si sin i si ọ̀kan ninu awọn ilú Gileadi.

Ibsani, Elonii ati Abdoni

8 Lẹhin rẹ̀ ni Ibsani ara Beti-lehemu ṣe idajọ Israeli. 9 O si lí ọgbọ̀n ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọbinrin ti on rán lọ si ode, o si fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin lati ode wá fi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún meje. 10 Ibsani si kú, a si sin i ni Beti-lehemu. 11 Lẹhin rẹ̀ ni Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni ṣe idajọ Israeli; on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹwa. 12 Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni si kú, a si sin i ni Aijaloni ni ilẹ Sebuluni. 13 Lẹhin rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hilleli, ti Piratoni, ṣe idajọ Israeli. 14 On si lí ogoji ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ ti ngùn ãdọrin ọmọ kẹtẹkẹtẹ: on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹjọ. 15 Abdoni ọmọ Hilleli ti Piratoni si kú, a si sin i ni Piratoni ni ilẹ Efraimu, li òke awọn Amaleki.

Onidajọ 13

Ìbí Samsoni

1 AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA; OLUWA si fi wọn lé awọn Filistini li ọwọ́ li ogoji ọdún. 2 Ọkunrin kan ara Sora si wà, ti iṣe idile Dani, orukọ rẹ̀ si ni Manoa, obinrin rẹ̀ si yàgan, kò si bimọ. 3 Angeli OLUWA si farahàn obinrin na, o si wi fun u pe, Sá kiyesi i, iwọ yàgan, iwọ kò si bimọ: ṣugbọn iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan. 4 Njẹ nitorina kiyesara, emi bẹ̀ ọ, máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, má si ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: 5 Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini. 6 Nigbana obinrin na wá, o si rò fun ọkọ rẹ̀, wipe, Enia Ọlọrun kan wá sọdọ mi, irí rẹ̀ si dabi irí angeli Ọlọrun, o ní ẹ̀ru gidigidi; ṣugbọn emi kò bilère ibiti o ti wá, bẹ̃li on kò si sọ orukọ rẹ̀ fun mi: 7 Ṣugbọn on sọ fun mi pe, Kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; nitorina má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni ki o má ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá titi di ọjọ́ ikú rẹ̀. 8 Nigbana ni Manoa bẹ̀ OLUWA, o si wipe, OLUWA, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki enia Ọlọrun, ti iwọ rán tun tọ̀ wa wá, ki o le kọ́ wa li ohun ti awa o ṣe si ọmọ na ti a o bi. 9 Ọlọrun si gbọ ohùn Manoa; angeli Ọlọrun na si tun tọ̀ obinrin na wá, bi on ti joko ninu oko; ṣugbọn Manoa ọkọ rẹ̀ kò sí nibẹ̀ pẹlu rẹ̀. 10 Obinrin na si yara kánkán, o si sure, o si sọ fun ọkọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Kiyesi i, ọkunrin ti o tọ̀ mi wá ni ijelo farahàn mi. 11 Manoa si dide, o si tẹle aya rẹ̀, o si wá sọdọ ọkunrin na, o si bi i pe, Iwọ li ọkunrin na ti o bá obinrin na sọ̀rọ? On si wipe, Emi ni. 12 Manoa si wipe, Njẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ: ìwa ọmọ na yio ti jẹ́, iṣẹ rẹ̀ yio ti jẹ́? 13 Angeli OLUWA si wi fun Manoa pe, Ni gbogbo eyiti mo sọ fun obinrin na ni ki o kiyesi. 14 Ki o má ṣe jẹ ohun kan ti o ti inu àjara wá, ki o má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ ohun aimọ́ kan; gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun u ni ki o kiyesi. 15 Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o da ọ duro, titi awa o si fi pèse ọmọ ewurẹ kan fun ọ. 16 Angeli OLUWA na si wi fun Manoa pe, Bi iwọ tilẹ da mi duro, emi ki yio jẹ ninu àkara rẹ: bi iwọ o ba si ru ẹbọ sisun kan, OLUWA ni ki iwọ ki o ru u si. Nitori Manoa kò mọ̀ pe angeli OLUWA ni iṣe. 17 Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Orukọ rẹ, nitori nigbati ọ̀rọ rẹ ba ṣẹ ki awa ki o le bọlá fun ọ? 18 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi, kiyesi i, Iyanu ni. 19 Manoa si mú ọmọ ewurẹ kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ, o si ru u lori apata kan si OLUWA: angeli na si ṣe ohun iyanu, Manoa ati obinrin rẹ̀ si nwò o. 20 O si ṣe ti ọwọ́-iná na nlọ soke ọrun lati ibi-pẹpẹ na wá, angeli OLUWA na si gòke ninu ọwọ́-iná ti o ti ibi-pẹpẹ jade wá. Manoa ati aya rẹ̀ si nwò o; nwọn si dojubolẹ. 21 Ṣugbọn angeli OLUWA na kò si tun farahàn fun Manoa tabi aya rẹ̀ mọ́. Nigbana ni Manoa to wa mọ̀ pe, angeli OLUWA ni iṣe. 22 Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun. 23 Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi. 24 Obinrin na si bi ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Samsoni: ọmọ na si dàgba, OLUWA si bukún u. 25 Ẹmi OLUWA si bẹ̀rẹsi ṣiṣẹ ninu rẹ̀ ni Mahane-dani, li agbedemeji Sora ati Eṣtaolu.

Onidajọ 14

Samsoni ati Ọmọbinrin Kan, Ará Timna

1 SAMSONI si sọkalẹ lọ si Timna, o si ri obinrin kan ni Timna ọkan ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini. 2 O si gòke wá, o si sọ fun baba on iya rẹ̀, o si wipe, Emi ri obinrin kan ni Timna ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini: njẹ nitorina ẹ fẹ́ ẹ fun mi li aya. 3 Nigbana ni baba on iya rẹ̀ wi fun u pe, Kò sí obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin awọn arakunrin rẹ, tabi ninu gbogbo awọn enia mi, ti iwọ fi nlọ ní obinrin ninu awọn alaikọlà Filistini? Samsoni si wi fun baba rẹ̀ pe, Fẹ́ ẹ fun mi; nitoripe o wù mi gidigidi. 4 Ṣugbọn baba ati iya rẹ̀ kò mọ̀ pe ati ọwọ́ OLUWA wá ni, nitoripe on nwá ọ̀na lati bá awọn Filistini jà. Nitoripe li akokò na awọn Filistini li alaṣẹ ni Israeli. 5 Nigbana ni Samsoni sọkalẹ lọ si Timna, ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀, o si dé ibi ọgbà-àjara ti o wà ni Timna: si kiyesi i, ẹgbọrọ kiniun kan nke ramuramu si i. 6 Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si fà a ya bi iba ti fà ọmọ-ewurẹ ya, bẹ̃ni kò sí nkan li ọwọ́ rẹ̀: on kò si sọ fun baba tabi iya rẹ̀ li ohun ti o ṣe. 7 On si sọkalẹ lọ, o si bá obinrin na sọ̀rọ; on si wù Samsoni gidigidi. 8 Lẹhin ijọ́ melokan o si tun pada lati mú obinrin na, o si yà lati wò okú kiniun na: si kiyesi i, ìṣu-ọ̀pọ oyin wà ninu okú kiniun na, ati oyin. 9 O si bù ninu rẹ̀ si ọwọ́ rẹ̀, o si njẹ ẹ li ajẹrìn, titi o si fi dé ọdọ baba ati iya rẹ̀, o si fi fun wọn, nwọn si jẹ: ṣugbọn on kò sọ fun wọn pe ninu okú kiniun li on ti mú oyin na wá. 10 Baba rẹ̀ si sọkalẹ tọ̀ obinrin na lọ: Samsoni si sè àse nibẹ̀; nitoripe bẹ̃li awọn ọmọkunrin ima ṣe. 11 O si ṣe nigbati nwọn ri i, nwọn si mú ọgbọ̀n enia wa bá a kẹgbẹ. 12 Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki npa alọ́ kan fun nyin: bi ẹnyin ba le já a fun mi titi ijọ́ meje àse yi, ti ẹnyin ba si mọ̀ ọ, njẹ emi o fun nyin li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ: 13 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba le já a fun mi, njẹ ẹnyin o fun mi li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ. Nwọn si wi fun u pe, Pa alọ́ rẹ ki awa ki o gbọ́. 14 O si wi fun wọn pe, Lati inu ọjẹun li onjẹ ti jade wá, ati lati inu alagbara li adùn ti jade wá. Nwọn kò si le já alọ́ na nìwọn ijọ́ mẹta. 15 O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn si wi fun obinrin Samsoni pe, Tàn ọkọ rẹ, ki o le já alọ́ na fun wa, ki awa ki o má ba fi iná sun iwọ ati ile baba rẹ: ẹnyin pè wa ki ẹnyin ki o le gbà ohun-iní wa ni? bẹ̃ ha kọ? 16 Obinrin Samsoni si sọkun niwaju rẹ̀, o si wipe, Iwọ korira mi ni, iwọ kò si fẹràn mi: iwọ pa alọ́ kan fun awọn ọmọ enia mi, iwọ kò si já a fun mi. On si wi fun u pe, Kiyesi i, emi kò já a fun baba ati iya mi, emi o ha já a fun ọ bi? 17 O si sọkun niwaju rẹ̀ titi ijọ́ meje ti àse na gbà: O si ṣe ni ijọ́ keje, o si já a fun u, nitoripe on ṣe e li aisimi pupọ̀, on si já alọ́ na fun awọn ọmọ enia rẹ̀. 18 Awọn ọkunrin ilunla na si wi fun u ni ijọ́ keje ki õrùn ki o to wọ̀ pe, Kili o dùn jù oyin lọ? kili o si lí agbara jù kiniun lọ? On si wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin kò fi ẹgbọrọ abo-malu mi tulẹ, ẹnyin kì ba ti mọ̀ alọ́ mi. 19 Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si sọkalẹ lọ si Aṣkeloni, o si pa ọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn, o si kò ẹrù wọn, o si fi ìparọ aṣọ fun awọn ti o já alọ́ na. Ibinu rẹ̀ si rú, on si gòke lọ si ile baba rẹ̀. 20 Nwọn si fi obinrin Samsoni fun ọkan ninu awọn ẹgbẹ rẹ̀, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀.

Onidajọ 15

1 O SI ṣe lẹhin ìgba diẹ, li akokò ikore alikama, Samsoni mú ọmọ ewurẹ kan lọ bẹ̀ aya rẹ̀ wò; on si wipe, Emi o wọle tọ̀ aya mi lọ ni iyẹwu. Ṣugbọn baba obinrin rẹ̀ kò jẹ ki o wọle. 2 Baba aya rẹ̀ si wipe, Nitõtọ emi ṣebi iwọ korira rẹ̀ patapata ni; nitorina ni mo ṣe fi i fun ẹgbẹ rẹ: aburò rẹ̀ kò ha ṣe arẹwà enia jù on lọ? mo bẹ̀ ọ, mú u dipò rẹ̀. 3 Samsoni si wi fun wọn pe, Nisisiyi emi o jẹ́ alaijẹbi lọdọ awọn Filistini, bi mo tilẹ ṣe wọn ni ibi. 4 Samsoni si lọ o mú ọdunrun kọ̀lọkọlọ, o si mú ètufu, o si fi ìru wọn kò ìru, o si fi ètufu kan sãrin ìru meji. 5 Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu. 6 Nigbana li awọn Filistini wipe, Tani ṣe eyi? Nwọn si dahùn pe, Samsoni, ana ara Timna ni, nitoriti o gbà obinrin rẹ̀, o si fi i fun ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Filistini si gòke wá, nwọn si fi iná sun obinrin na ati baba rẹ̀. 7 Samsoni si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin ba ṣe irú eyi, dajudaju emi o gbẹsan lara nyin, lẹhin na emi o si dẹkun. 8 On si kọlù wọn, o si pa wọn ni ipakupa: o si sọkalẹ o si joko ni pàlàpálá apata Etamu.

Samsoni Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia

9 Nigbana li awọn Filistini gòke lọ, nwọn si dótì Juda, nwọn si tẹ́ ara wọn lọ bẹrẹ ni Lehi. 10 Awọn ọkunrin Juda si wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe gòke tọ̀ wa wá? Nwọn si dahùn wipe, Lati dè Samsoni li awa ṣe wá, lati ṣe si i gẹgẹ bi on ti ṣe si wa. 11 Nigbana li ẹgbẹdogun ọkunrin Juda sọkalẹ lọ si palapala apata Etamu, nwọn si wi fun Samsoni, pe, Iwọ kò mọ̀ pe awọn Filistini li alaṣẹ lori wa? kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? On si wi fun wọn pe, Gẹgẹ bi nwọn ti ṣe si mi, bẹ̃li emi ṣe si wọn. 12 Nwọn si wi fun u pe, Awa sọkalẹ wá lati dè ọ, ki awa ki o le fi ọ lé awọn Filistini lọwọ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ bura fun mi, pe ẹnyin tikara nyin ki yio pa mi. 13 Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá. 14 Nigbati o dé Lehi, awọn Filistini hó bò o: ẹmi OLUWA si bà lé e, okùn ti o si wà li apa rẹ̀ si wa dabi okùn-ọ̀gbọ ti o ti jóna, ìde rẹ̀ si tú kuro li ọwọ́ rẹ̀. 15 O si ri pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ titun kan, o si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si fi i pa ẹgbẹrun ọkunrin. 16 Samsoni si wipe, Pari-ẹrẹkẹ kan ni mo fi pa òkiti kan, òkiti meji; pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ kan ni mo fi pa ẹgbẹrun ọkunrin. 17 O si ṣe, nigbati o pari ọ̀rọ isọ tán, o sọ pari-ẹrẹkẹ na nù, o si pè ibẹ̀ na ni Ramati-lehi. 18 Ongbẹ si ngbẹ ẹ gidigidi, o si kepè OLUWA, wipe, Iwọ ti fi ìgbala nla yi lé ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ: nisisiyi emi o kú nitori ongbẹ, emi o si bọ́ si ọwọ́ awọn alaikọlà. 19 Ṣugbọn Ọlọrun si là ibi kòto kan ti o wà ni Lehi, nibẹ̀ li omi si sun jade; nigbati on si mu u tán ẹmi rẹ̀ si tun pada, o si sọjí: nitorina ni a ṣe pè orukọ ibẹ̀ na ni Eni-hakkore, ti o wà ni Lehi, titi o fi di oni-oloni. 20 On si ṣe idajọ Israeli li ọjọ́ awọn Filistini li ogún ọdún.

Onidajọ 16

Samsoni ní Ìlú Gasa

1 SAMSONI si lọ si Gasa, o si ri obinrin panṣaga kan nibẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ. 2 Awọn ara Gasa si gbọ́ pe, Samsoni wá si ihin. Nwọn si yi i ká, nwọn lùmọ́ ni gbogbo oru na li ẹnu-bode ilu na, nwọn si dakẹ jẹ ni gbogbo oru na, wipe, Li owurọ̀ nigbati ilẹ ba mọ́, li awa a pa a. 3 Samsoni si dubulẹ titi o fi di ãrin ọganjọ, o si dide lãrin ọganjọ, o si gbé ilẹkun-ibode ilu na, ati opó mejeji, o si fà wọn tu pẹlu idabu-ilẹ̀kùn, o gbé wọn lé ejika rẹ̀, o si rù wọn lọ si ori òke kan ti o wà niwaju Hebroni.

Samsoni ati Delila

4 O si ṣe lẹhin eyinì, o si fẹ́ obinrin kan li afonifoji Soreki, a si ma pè orukọ rẹ̀ ni Delila. 5 Awọn ijoye Filistini tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Tàn a, ki o si mọ̀ ibiti agbara nla rẹ̀ gbé wà, ati bi awa o ti ṣe le bori rẹ̀, ki awa ki o le dè e lati jẹ ẹ niyà: olukuluku wa yio si fun ọ ni ẹdẹgbẹfa owo fadakà. 6 Delila si wi fun Samsoni pe, Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi, nibo li agbara nla rẹ gbé wà, ati kili a le fi dè ọ lati jẹ ọ niyà. 7 Samsoni si wi fun u pe, Bi a ba fi okùn tutù meje ti a kò ságbẹ dè mi, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran. 8 Nigbana li awọn ijoye Filistini mú okùn tutù meje tọ̀ ọ wá ti a kò ságbẹ, o si fi okùn wọnni dè e. 9 Obinrin na si ní awọn kan, ti nwọn lumọ́ ninu yará. On si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. On si já okùn na, gẹgẹ bi owú ti ijá nigbati o ba kan iná. Bẹ̃li a kò mọ̀ agbara rẹ̀. 10 Delila si wi fun Samsoni pe, Kiyesi i, iwọ tàn mi jẹ, o si purọ́ fun mi: wi fun mi, emi bẹ̀ ọ, kili a le fi dè ọ. 11 On si wi fun u pe, Bi nwọn ba le fi okùn titun ti a kò ti lò rí dè mi le koko, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran. 12 Bẹ̃ni Delila mú okùn titun, o si fi dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. Awọn ti o lumọ́ dè e wà ninu yará. On si já wọn kuro li apa rẹ̀ bi owu. 13 Delila si wi fun Samsoni pe, Titi di isisiyi iwọ ntàn mi ni, iwọ si npurọ́ fun mi: sọ fun mi, kili a le fi dè ọ. On si wi fun u pe, Bi iwọ ba wun ìdi irun meje ti o wà li ori mi. 14 On si fi ẽkàn dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju orun rẹ̀, o si fà ẽkàn ìti na pẹlu ihunṣọ rẹ̀ lọ. 15 On si wi fun u pe, Iwọ ha ti ṣe wipe, Emi fẹ́ ọ, nigbati ọkàn rẹ kò ṣedede pẹlu mi? iwọ ti tàn mi ni ìgba mẹta yi, iwọ kò si sọ ibiti agbara nla rẹ gbé wà fun mi. 16 O si ṣe, nigbati o fi ọ̀rọ rẹ̀ rọ̀ ọ li ojojumọ́, ti o si ṣe e laisimi, tobẹ̃ ti sũru fi tan ọkàn rẹ̀ dé ikú. 17 Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran. 18 Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn. 19 O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀. 20 On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on. 21 Awọn Filistini sì mú u, nwọn si yọ ọ li oju mejeji; nwọn si mú u sọkalẹ wá si Gasa, nwọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ̀ idẹ dè e: on si nlọ-ọlọ ni ile-tubu. 22 Ṣugbọn irun ori rẹ̀ bẹ̀rẹsi hù lẹhin igbati a ti fá a tán.

Ikú Samsoni

23 Nigbana ni awọn ijoye Filistini kó ara wọn jọ lati ru ẹbọ nla kan si Dagoni oriṣa wọn, ati lati yọ̀: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi Samsoni ọtá wa lé wa lọwọ. 24 Nigbati awọn enia si ri i, nwọn fi iyin fun oriṣa wọn: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi ọtá wa lé wa lọwọ, ẹniti npa ilẹ wa run, ti o si pa ọ̀pọlọpọ enia ninu wa. 25 O si ṣe, nigbati inu wọn dùn, ni nwọn wipe, Ẹ pè Samsoni, ki o wa ṣiré fun wa. Nwọn si pè Samsoni lati inu ile-itubu wá; o si ṣiré niwaju wọn: nwọn si mu u duro lãrin ọwọ̀n meji. 26 Samsoni si wi fun ọmọkunrin ti o di ọwọ́ rẹ̀ mú pe, Jẹ ki emi ki o fọwọbà awọn ọwọ̀n ti ile joko lé, ki emi ki o le faratì wọn. 27 Njẹ ile na kún fun ọkunrin ati obinrin; gbogbo awọn ijoye Filistini si wà nibẹ̀; awọn ti o si wà lori orule, ati ọkunrin ati obinrin, o to ìwọn ẹgbẹdogun enia, ti nworan Samsoni nigbati o nṣiré. 28 Samsoni si kepè OLUWA, o si wipe, Oluwa ỌLỌRUN, emi bẹ̀ ọ, ranti mi, ki o si jọ̃ fun mi li agbara lẹ̃kanṣoṣo yi, Ọlọrun, ki emi ki o le gbẹsan lẹ̃kan lara awọn Filistini nitori oju mi mejeji. 29 Samsoni si dì ọwọ̀n ãrin mejeji na mú lori eyiti ile na joko, o si faratì wọn, o fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú kan, o si fi ọwọ́ òsi rẹ̀ mú ekeji. 30 Samsoni si wipe, Jẹ ki nkú pẹlu awọn Filistini. O si fi gbogbo agbara rẹ̀ bẹ̀rẹ; ile na si wó lù awọn ijoye wọnni, ati gbogbo enia ti o wà ninu rẹ̀. Bẹ̃li awọn okú ti o pa ni ikú rẹ̀, pọjù awọn ti o pa li ãyè rẹ̀ lọ. 31 Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo idile baba rẹ̀ sọkalẹ wá, nwọn si gbé e gòke, nwọn si sin i lãrin Sora on Eṣtaolu ni ibojì Manoa baba rẹ̀. O si ṣe idajọ Israeli li ogún ọdún.

Onidajọ 17

Ère Mika

1 ỌKUNRIN kan si wà ni ilẹ òke Efraimu, orukọ ẹniti ijẹ Mika. 2 On si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẹdẹgbẹfa owo fadakà ti a kólọ lọwọ rẹ, nitori eyiti iwọ gegún, ti iwọ si sọ̀rọ rẹ̀ li etí mi pẹlu, kiyesi i, fadakà na wà li ọwọ́ mi; emi li o kó o. Iya rẹ̀ si wipe, Alabukún ti OLUWA ni ọmọ mi. 3 On si kó ẹdẹgbẹfa owo fadakà na fun iya rẹ̀ pada, iya rẹ̀ si wipe, Patapata ni mo yà fadakà wọnni sọ̀tọ fun OLUWA kuro li ọwọ́ mi, fun ọmọ mi, lati fi ṣe ere fifin ati ere didà: njẹ nitorina emi o fun ọ pada. 4 Ṣugbọn o kó owo na pada fun iya rẹ̀; iya rẹ̀ si mú igba owo fadakà, o si fi i fun oniṣọnà, ẹniti o fi i ṣe ere fifin ati ere didà: o si wà ni ile Mika. 5 Ọkunrin na Mika si ní ile-oriṣa kan, o si ṣe efodu, ati terafimu, o si yà ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sọtọ̀, ẹniti o si wa di alufa rẹ̀. 6 Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀. 7 Ọmọkunrin kan si ti Beti-lehemu-juda wá, ti iṣe idile Juda, ẹniti iṣe ẹ̀ya Lefi, on si ṣe atipo nibẹ̀. 8 Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ. 9 Mika si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si wi fun u pe, Ẹ̀ya Lefi ti Beti-lehemu-juda li emi iṣe, emi si nlọ ṣe atipo nibikibi ti emi ba ri. 10 Mika si wi fun u pe, Bá mi joko, ki iwọ ki o ma ṣe baba ati alufa fun mi, emi o ma fi owo fadakà mẹwa fun ọ li ọdún, adápe aṣọ kan, ati onjẹ rẹ. Bẹ̃ni ọmọ Lefi na si wọle. 11 O si rọ̀ ọmọ Lefi na lọrùn lati bá ọkunrin na joko; ọmọkunrin na si wà lọdọ rẹ̀ bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀. 12 Mika si yà ọmọ Lefi na sọ̀tọ, ọmọkunrin na si wa di alufa rẹ̀, o si wà ninu ile Mika. 13 Mika si wipe, Njẹ nisisiyi li emi tó mọ̀ pe, OLUWA yio ṣe mi li ore, nitoriti emi li ọmọ Lefi kan li alufa mi.

Onidajọ 18

Mika ati Ẹ̀yà Dani

1 LI ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: ati li ọjọ́ wọnni ẹ̀ya Dani nwá ilẹ-iní kan lati joko si; nitoripe titi o fi di ọjọ́ na, ilẹ-iní wọn lãrin awọn ẹ̀ya Israeli kò ti ibọ́ si ọwọ́ wọn. 2 Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀. 3 Nigbati nwọn wà leti ile Mika, nwọn si mọ̀ ohùn ọmọkunrin Lefi na: nwọn si wọ̀ inu ile na, nwọn si wi fun u pe, Tali o mú ọ wá ihinyi? kini iwọ si nṣe ni ihinyi? kini iwọ si ní nihin? 4 On si wi fun wọn pe, Bayibayi ni Mika ṣe fun mi, o gbà mi si iṣẹ, alufa rẹ̀ li emi si iṣe. 5 Nwọn si wi fun u pe, Bère lọdọ Ọlọrun, awa bẹ̀ ọ, ki awa ki o le mọ̀ bi ọ̀na wa ti awa nlọ yio jasi rere. 6 Alufa na si wi fun wọn pe, Ẹ ma lọ li alafia: ọ̀na nyin ti ẹnyin nlọ mbẹ niwaju OLUWA. 7 Nigbana li awọn ọkunrin mararun na lọ, nwọn si dé Laiṣi, nwọn si ri awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, bi nwọn ti joko laibẹ̀ru, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Sidoni, ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru; kò si sí olori kan ni ilẹ na, ti iba mu oju tì wọn li ohunkohun, nwọn si jìna si awọn ara Sidoni, nwọn kò si ba ẹnikẹni ṣe. 8 Nwọn si wá sọdọ awọn arakunrin wọn si Sora ati Eṣtaolu: awọn arakunrin wọn si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin wi? 9 Nwọn si wipe, Ẹ dide, ki awa ki o tọ̀ wọn: nitoriti awa ri ilẹ na, si kiyesi i, o dara gidigidi: ẹ dakẹ ni? ẹ má ṣe lọra lati lọ, ati lati wọ̀ ibẹ̀ lọ gbà ilẹ na. 10 Nigbati ẹnyin ba lọ, ẹnyin o dé ọdọ awọn enia ti o wà laibẹ̀ru, ilẹ na si tobi: nitoriti Ọlọrun ti fi i lé nyin lọwọ; ibiti kò sí ainí ohunkohun ti mbẹ lori ilẹ. 11 Awọn enia idile Dani si ti ibẹ̀ lọ, lati Sora ati lati Eṣtaolu, ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun; 12 Nwọn si gòke lọ, nwọn si dó si Kiriati-jearimu, ni Juda: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ̀ na ni Mahane-dani titi o fi di oni yi: kiyesi i, o wà lẹhin Kiriati-jearimu. 13 Nwọn si kọja lati ibẹ̀ lọ si ilẹ òke Efraimu, nwọn si wá si ile Mika. 14 Nigbana li awọn ọkunrin marun ti a rán ti o ti lọ ṣe amí ilẹ Laiṣi dahùn, nwọn si wi fun awọn arakunrin wọn pe, Ẹ mọ̀ pe efodu kan wà ninu ile wọnyi, ati terafimu, ati ere fifin, ati ere didà? njẹ nitorina ẹ rò eyiti ẹnyin o ṣe. 15 Nwọn si yà sibẹ̀, nwọn si wá si ile ọmọkunrin Lefi na, ani si ile Mika, nwọn si bère alafia rẹ̀. 16 Awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun ninu awọn ọmọ Dani, duro li ẹnu-ọ̀na. 17 Awọn ọkunrin marun ti o ti lọ iṣe amí ilẹ na gòke lọ, nwọn si wá si ibẹ̀ na, nwọn si kó ere fifin, ati efodu, ati terafimu, ati ere didà na: alufa na si duro li ẹnu-ọ̀na pẹlu awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun. 18 Nigbati awọn wọnyi si wọ̀ ile Mika lọ, nwọn si mú ere fifin, efodu, ati terafimu, ati ere didà na, nigbana li alufa na wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe yi? 19 Nwọn si wi fun u pe, Dakẹ, fi ọwọ́ rẹ lé ẹnu rẹ, ki o si ma bá wa lọ, ki o si ma ṣe baba fun wa ati alufa: o ha san fun ọ lati ṣe alufa fun ile ọkunrin kan, tabi ki iwọ ki o ṣe alufa fun ẹ̀ya ati idile kan ni Israeli? 20 Inu alufa na si dùn, o si mú efodu, ati terafimu, ati ere fifin, o si bọ̀ sãrin awọn enia na. 21 Bẹ̃ni nwọn yipada nwọn si lọ, nwọn tì awọn ọmọ kekere ati ẹran ati ẹrù siwaju wọn. 22 Nigbati nwọn si lọ jìna si ile Mika, awọn ọkunrin ti o wà ninu ile wọnni ti o sunmọ ile Mika kó ara wọn jọ, nwọn si lé awọn ọmọ Dani bá. 23 Nwọn si kọ si awọn ọmọ Dani. Nwọn si yi oju wọn pada, nwọn wi fun Mika pe, Kili o ṣe ọ, ti iwọ fi kó irú ẹgbẹ bẹ̃ lẹhin wá? 24 On si wipe, Ẹnyin kó awọn oriṣa mi ti mo ṣe lọ, ẹ si mú alufa, ẹ si lọ, kini mo si tun ní? kili eyiti ẹnyin wi fun mi pe, Kili o ṣe ọ? 25 Awọn ọmọ Dani si wi fun u pe, Máṣe jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ lãrin wa, ki awọn oninuṣùṣu ki o má bã kọlù nyin, iwọ a si sọ ẹmi rẹ nù, ati ẹmi awọn ara ile rẹ. 26 Awọn ọmọ Dani si ba ọ̀na wọn lọ: nigbati Mika si ri i pe, nwọn lagbara jù on lọ, on si yipada, o si pada lọ sinu ile rẹ̀. 27 Nwọn si kó awọn nkan wọnni ti Mika ṣe, ati alufa ti o ní, nwọn si wá si Laiṣi sọdọ awọn enia ti o wà ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru, nwọn si fi oju idà kọlù wọn, nwọn si fi iná kun ilu na. 28 Kò si sí olugbala, nitoriti o jìna si Sidoni, nwọn kò si bá ẹnikẹni ṣe; o si wà ni afonifoji ti o wà ni Beti-rehobu. Nwọn si kọ́ ilu na, nwọn si ngbé inu rẹ̀. 29 Nwọn si pè orukọ ilu na ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn, ẹniti a bi fun Israeli: ṣugbọn Laiṣi li orukọ ilu na li atijọ rí. 30 Awọn ọmọ Dani si gbé ere fifin na kalẹ: ati Jonatani, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, on ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin li o nṣe alufa fun ẹ̀ya Dani titi o fi di ọjọ́ ti a fi kó ilẹ na ni igbekun lọ. 31 Nwọn si gbé ere fifin ti Mika ṣe kalẹ ni gbogbo ọjọ́ ti ile Ọlọrun fi wà ni Ṣilo.

Onidajọ 19

Ọmọ Lefi Kan ati Obinrin Rẹ̀

1 O si ṣe li ọjọ́ wọnni, nigbati kò sí ọba kan ni Israeli, ọkunrin Lefi kan nṣe atipo ni ìha ọhún ilẹ òke Efraimu, ẹniti o si mú àle kan lati Beti-lehemu-juda wá. 2 Àle rẹ̀ na si ṣe panṣaga si i, o si lọ kuro lọdọ rẹ̀ si ile baba rẹ̀ si Beti-lehemu-juda, o si wà ni ibẹ̀ ni ìwọn oṣù mẹrin. 3 Ọkọ rẹ̀ si dide, o si tọ̀ ọ lọ, lati tù u ninu, ati lati mú u pada, ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mbẹ pẹlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ meji: ọmọbinrin na si mú u wá sinu ile baba rẹ̀: nigbati baba rẹ̀ si ri i, o yọ̀ lati pade rẹ̀. 4 Ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si da a duro; o si bá a joko ni ijọ́ mẹta; nwọn jẹ nwọn mu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀. 5 O si ṣe ni ijọ́ kẹrin, nwọn jí ni kùtukutu, o si dide lati lọ: baba ọmọbinrin na si wi fun ana rẹ̀ pe, Fi òkele onjẹ kan tẹlẹ inu, lẹhin na ki ẹ ma lọ. 6 Nwọn si joko, awọn mejeji si jùmọ jẹ, nwọn si mu: baba ọmọbinrin na si wi fun ọkunrin na pe, Mo bẹ̀ ọ, farabalẹ, ki o si duro li oru oni, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn. 7 Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, ana rẹ̀ si rọ̀ ọ, o si tun sùn sibẹ̀. 8 On si dide ni kùtukutu ọjọ́ karun lati lọ, baba ọmọbinrin na si wipe, Mo bẹ̀ ọ, tù ara rẹ lara, ki ẹ si duro titi di irọlẹ; awọn mejeji si jẹun. 9 Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, on, ati àle rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀, ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ọjọ́ di aṣalẹ tán, emi bẹ̀ ọ duro li oru yi: kiyesi i ọjọ́ lọ tán, sùn sihin, ki inu rẹ ki o le dùn: ni kùtukutu ọla ẹ tète bọ́ si ọ̀na nyin, ki iwọ ki o le lọ ile. 10 Ọkunrin na si kọ̀ lati sùn, o si dide o si lọ, o si dé ọkankan Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): kẹtẹkẹtẹ meji ti a dì ni gãri wà lọdọ rẹ̀, àle rẹ̀ pẹlu si wà lọdọ rẹ̀. 11 Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀. 12 Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, Awa ki o yà si ilu ajeji kan, ti ki iṣe ti awọn ọmọ Israeli; awa o rekọja si Gibea. 13 On si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Wá jẹ ki a sunmọ ọkan ninu ibi wọnyi; ki a si wọ̀ si Gibea, tabi Rama. 14 Nwọn si rekọja, nwọn lọ: õrùn si wọ̀ bá wọn leti Gibea, ti iṣe ti Benjamini. 15 Nwọn si yà si Gibea lati wọ̀ ọ, ati lati sùn nibẹ̀: o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, o joko ni igboro ilu na: nitoriti kò sí ẹnikan ti o gbà wọn sinu ile rẹ̀ lati wọ̀. 16 Si kiyesi, i ọkunrin arugbo kan si nti ibi iṣẹ rẹ̀ bọ̀ lati inu oko wá li alẹ; ọkunrin na jẹ́ ara ilẹ òke Efraimu pẹlu, on si ṣe atipo ni Gibea: ṣugbọn ẹ̀ya Benjamini ni awọn ọkunrin ibẹ̀ iṣe. 17 Nigbati o gbé oju rẹ̀ soke, o si ri èro kan ni igboro ilu; ọkunrin arugbo na si wipe, Nibo ni iwọ nrè? nibo ni iwọ si ti wá? 18 On si wi fun u pe, Awa nrekọja lati Beti-lehemu-juda lọ si ìha ọhùn ilẹ òke Efraimu; lati ibẹ̀ li emi ti wá, emi si ti lọ si Beti-lehemu-juda: nisisiyi emi nlọ si ile OLUWA; kò si sí ẹnikan ti o gbà mi si ile. 19 Bẹ̃ni koriko ati ohunjijẹ mbẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ wa; onjẹ ati ọti-waini si mbẹ fun mi pẹlu, ati fun iranṣẹbinrin rẹ, ati fun ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ awọn iranṣẹ rẹ: kò si sí ainí ohunkohun. 20 Ọkunrin arugbo na si wipe, Alafia fun ọ; bi o ti wù ki o ri, jẹ ki gbogbo ainí rẹ ki o pọ̀ si apa ọdọ mi; ọkanṣoṣo ni, máṣe sùn si igboro. 21 Bẹ̃li o mú u wá sinu ile rẹ̀, o si fi onjẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ: nwọn wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, nwọn jẹ nwọn si mu. 22 Njẹ bi nwọn ti nṣe ariya, kiyesi i, awọn ọkunrin ilu na, awọn ọmọ Beliali kan, yi ile na ká, nwọn si nlù ilẹkun; nwọn si sọ fun bale ile na ọkunrin arugbo nì, pe, Mú ọkunrin ti o wọ̀ sinu ile rẹ nì wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ. 23 Ọkunrin, bale ile na si jade tọ̀ wọn lọ, o si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ẹnyin arakunrin mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ má ṣe hùwa buburu; nitoriti ọkunrin yi ti wọ̀ ile mi, ẹ má ṣe hùwa wère yi. 24 Kiyesi i, ọmọbinrin mi li eyi, wundia, ati àle rẹ̀; awọn li emi o mú jade wá nisisiyi, ki ẹnyin tẹ́ wọn li ogo, ki ẹnyin ṣe si wọn bi o ti tọ́ li oju nyin: ṣugbọn ọkunrin yi ni ki ẹnyin má ṣe hùwa wère yi si. 25 Ṣugbọn awọn ọkunrin na kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀: ọkunrin na si mú àle rẹ̀, o si mú u tọ̀ wọn wá; nwọn si mọ̀ ọ, nwọn si hù u niwakiwa ni gbogbo oru na, titi o fi di owurọ̀: nigbati o si di afẹmọjumọ́ nwọn jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. 26 Nigbana li obinrin na wá li àfẹmọjumọ́, o si ṣubu lulẹ, li ẹnu-ilẹkun ile ọkunrin na nibiti oluwa rẹ̀ gbé wà, titi ilẹ fi mọ́. 27 Oluwa rẹ̀ si dide li owurọ̀, o si ṣi ilẹkun ile na, o si jade lati ba ọ̀na rẹ̀ lọ: si kiyesi i obinrin na, àle rẹ̀, ṣubu lulẹ li ẹnu-ilẹkun ile na, ọwọ́ rẹ̀ si wà li ẹnu-ọ̀na na. 28 On si wi fun u pe, Dide, jẹ ki a ma lọ; ṣugbọn kò sí ẹniti o dahùn: nigbana li ọkunrin na si gbé e lé ori kẹtẹkẹtẹ, ọkunrin na si dide, o si lọ si ilu rẹ̀. 29 Nigbati o dé ile rẹ̀, on si mú ọbẹ, o si mú àle rẹ̀ na, o si kun u ni-ike-ni-ike, o si pín i si ọ̀na mejila, o si rán a lọ si gbogbo àgbegbe Israeli. 30 O si ṣe, ti gbogbo awọn ẹniti o ri i wipe, A kò ti ìhu irú ìwa bayi, bẹ̃li a kò ti iri i lati ọjọ́ ti awọn ọmọ Israeli ti gòke ti ilẹ Egipti wá titi o fi di oni-oloni: ẹ rò o, ẹ gbimọ̀, ki ẹ si sọ̀rọ.

Onidajọ 20

Israẹli Múra Ogun

1 NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa. 2 Awọn olori gbogbo enia na, ani ti gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, si pésẹ̀ larin ijọ awọn enia Ọlọrun, ogún ọkẹ ọkunrin ẹlẹsẹ̀ ti o kọ idà. 3 (Awọn ọmọ Benjamini si gbọ́ pe awọn ọmọ Israeli gòke lọ si Mispa.) Awọn ọmọ Israeli si wipe, Sọ fun wa, bawo ni ti ìwabuburu yi ti ri? 4 Ọkunrin Lefi na, bale obinrin na ti a pa, dahùn wipe, Mo wá si Gibea ti iṣe ti Benjamini, emi ati àle mi, lati wọ̀. 5 Awọn ọkunrin Gibea si dide si mi, nwọn si yi ile na ká mọ́ mi li oru; nwọn si rò lati pa mi, nwọn si ba àle mi ṣe iṣekuṣe, o si kú. 6 Mo si mú àle mi, mo ke e wẹ́wẹ, mo si rán a lọ si gbogbo ilẹ-iní Israeli: nitoriti nwọn hù ìwakiwa ati ìwa wère ni Israeli. 7 Kiyesi i, ọmọ Israeli ni gbogbo nyin ṣe, ẹ mú èro ati ìmọran nyin wá. 8 Gbogbo awọn enia na si dide bi ọkunrin kan, wipe, Kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio wọ̀ inu agọ́ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni kò sí ẹnikẹni ti yio pada si ile rẹ̀. 9 Ṣugbọn nisisiyi eyi li ohun ti a o ṣe si Gibea; awa ṣẹ keké, awa o si gòke lọ sibẹ̀; 10 Awa o si mú ọkunrin mẹwa ninu ọgọrun jalẹ ni gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, ati ọgọrun ninu ẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun ninu ẹgbãrun, lati mú onjẹ fun awọn enia na wá, ki nwọn ki o le ṣe, nigbati nwọn ba dé Gibea ti Benjamini, gẹgẹ bi gbogbo ìwa-wère ti nwọn hù ni Israeli. 11 Bẹ̃ni gbogbo ọkunrin Israeli dó tì ilu na, nwọn fi ìmọ ṣọkan bi enia kan. 12 Awọn ẹ̀ya Israeli si rán ọkunrin si gbogbo ẹ̀ya Benjamini, wipe, Ìwa buburu kili eyiti a hù lãrin nyin yi? 13 Njẹ nisisiyi ẹ mu awọn ọkunrin na fun wa wá, awọn ọmọ Beliali, ti nwọn wà ni Gibea, ki awa ki o le pa wọn, ki awa ki o le mú ìwabuburu kuro ni Israeli. Ṣugbọn awọn ọmọ Benjamini kò fẹ́ fetisi ohùn awọn ọmọ Israeli awọn arakunrin wọn. 14 Awọn ọmọ Benjamini si kó ara wọn jọ lati ilu wọnni wá si Gibea, lati jade lọ ibá awọn ọmọ Israeli jagun. 15 A si kà awọn ọmọ Benjamini li ọjọ́ na, lati ilu wọnni wá, nwọn jẹ́ ẹgbã mẹtala ọkunrin ti nkọ idà, lẹhin awọn ara Gibea ti a kà, ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin. 16 Ninu gbogbo awọn enia yi, a ri ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin aṣòsi; olukuluku wọn le gbọ̀n kànakana ba fọnrán owu li aitase. 17 Ati awọn ọkunrin Israeli, li àika Benjamini, si jẹ́ ogún ọkẹ enia ti o nkọ idà: gbogbo awọn wọnyi si jẹ́ ologun.

Israẹli Bá Ẹ̀yà Bẹnjamini Jagun

18 Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si lọ si Beti-eli nwọn si bère lọdọ Ọlọrun, wipe, Tani ninu wa ti yio tètekọ gòke lọ ibá awọn ọmọ Benjamini jà? OLUWA si wipe, Juda ni yio tète gòke lọ. 19 Awọn ọmọ Israeli si dide li owurọ̀, nwọn si dótì Gibea. 20 Awọn ọkunrin Israeli si jade lọ ibá Benjamini jà; awọn ọkunrin Israeli si tẹ́gun dè wọn ni Gibea. 21 Awọn ọmọ Benjamini si ti Gibea jade wá, nwọn si pa ẹgba mọkanla enia ninu awọn ọmọ Israeli. 22 Awọn enia na, awọn ọkunrin Israeli si gbà ara wọn niyanju, nwọn si tun tẹ́gun ni ibi ti nwọn kọ́ tẹ́gun si ni ijọ́ kini. 23 (Awọn ọmọ Israeli si gòke lọ, nwọn si sọkun niwaju OLUWA titi di aṣalẹ, nwọn si bère lọdọ OLUWA wipe, Ki emi ki o si tun lọ ibá awọn ọmọ Benjamini arakunrin mi jà bi? OLUWA si wipe, Ẹ gòke tọ̀ ọ.) 24 Awọn ọmọ Israeli si sunmọ awọn ọmọ Benjamini ni ijọ́ keji. 25 Benjamini si jade si wọn lati Gibea wa ni ijọ́ keji, nwọn si pa ninu awọn ọmọ Israeli ẹgba mẹsan ọkunrin; gbogbo awọn wọnyi li o nkọ idà. 26 Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati gbogbo awọn enia na gòke lọ, nwọn wá si Beti-eli, nwọn sọkun, nwọn si joko nibẹ̀ niwaju OLUWA, nwọn si gbàwẹ li ọjọ́ na titi di aṣalẹ; nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju OLUWA. 27 Awọn ọmọ Israeli si bère lọdọ OLUWA, (nitori ti apoti majẹmu Ọlọrun mbẹ nibẹ̀ li ọjọ́ wọnni. 28 Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni si nduro niwaju rẹ̀ li ọjọ́ wọnni,) wipe, Ki emi ki o ha si tun gbogun jade si Benjamini arakunrin mi bi? tabi ki emi ki o dẹkun? OLUWA si wipe, Ẹ gòke lọ; nitoripe li ọla emi o fi i lé ọ lọwọ. 29 Israeli si yàn awọn enia ti o ba yi Gibea ká. 30 Awọn ọmọ Israeli si gòke tọ̀ awọn ọmọ Benjamini lọ ni ijọ́ kẹta, nwọn si tẹ́gun si Gibea, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. 31 Awọn ọmọ Benjamini si jade tọ̀ awọn enia na lọ, a si fà wọn kuro ni ilu; nwọn si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn enia, nwọn npa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju; li opópo wọnni ti o lọ si Beti-eli, ati ekeji si Gibea, ni pápa, nwọn pa ìwọn ọgbọ̀n ọkunrin ninu Israeli. 32 Awọn ọmọ Benjamini si wipe, A lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli wipe, Ẹ jẹ ki a sá, ki a si fà wọn kuro ni ìlú si opópo. 33 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si dide kuro ni ipò wọn, nwọn si tẹ́gun ni Baali-tamari: awọn ti o wà ni ibuba ninu awọn enia Israeli si dide kuro ni ipo wọn, lati pápa Gibea wá. 34 Ẹgba marun ọkunrin ti a ti yàn ninu gbogbo Israeli si lọ si Gibea, ìja na si le gidigidi: ṣugbọn nwọn kò si mọ̀ pe ibi sunmọ wọn. 35 OLUWA si kọlù Benjamini niwaju Israeli: awọn ọmọ Israeli si pa ẹgba mejila ọkunrin o le ẹdẹgbẹfa li ọjọ́ na ninu awọn enia Benjamini: gbogbo awọn wọnyi li o kọ́ idà.

Ìṣẹ́gun Israẹli

36 Bẹ̃li awọn ọmọ Benjamini wa ri pe a ṣẹgun wọn: nitoriti awọn ọkunrin Israeli bìsẹhin fun awọn ara Benjamini nitoriti nwọn gbẹkẹle awọn ti o wà ni ibùba, ti nwọn yàn si eti Gibea. 37 Awọn ti o wà ni ibùba si yára, nwọn rọ́wọ̀ Gibea; awọn ti o wà ni ibuba si papọ̀, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu na. 38 Njẹ àmi ti o wà lãrin awọn ọkunrin Israeli, ati awọn ti o wà ni ibùba ni pe, ki nwọn jẹ ki ẹ̃fi nla ki o rú soke lati ilu na wá. 39 Nigbati awọn ọkunrin Israeli si pẹhinda ni ibi ìja na, Benjamini si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn ọkunrin Israeli, o si pa bi ọgbọ̀n enia: nitoriti nwọn wipe, Nitõtọ a lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìja iṣaju. 40 Ṣugbọn nigbati awọsanma bẹ̀rẹsi rú soke lati ilu na wá pẹlu gọ́gọ ẹ̃fi, awọn ara Benjamini wò ẹhin wọn, si kiyesi i, ẹ̃fi gbogbo ilu na gòke lọ si ọrun. 41 Awọn ọkunrin Israeli si yipada, awọn ọkunrin Benjamini si damu: nitoriti nwọn ri pe ibi déba wọn. 42 Nitorina, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọkunrin Israeli si ọ̀na ijù; ṣugbọn ogun na lepa wọn kikan; ati awọn ti o ti ilu wọnni jade wá ni nwọn pa lãrin wọn. 43 Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn. 44 Ẹgba mẹsan ọkunrin li o si ṣubu ninu awọn enia Benjamini, gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin. 45 Nwọn si yipada nwọn sálọ si ìha ijù sori okuta Rimmoni: nwọn si ṣà ẹgbẹdọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn li opópo; nwọn lepa wọn kikan dé Gidomu, nwọn si pa ẹgba ọkunrin ninu wọn. 46 Bẹ̃ni gbogbo awọn ni o ṣubu ni ijọ́ na ninu awọn ara Benjamini jẹ́ ẹgba mejila ọkunrin o le ẹgbẹrun ti o nkọ idà; gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin. 47 Ṣugbọn ẹgbẹta ọkunrin yipada, nwọn si sá si ìha ijù si ibi okuta Rimmoni, nwọn si joko sinu okuta Rimmoni li oṣù mẹrin. 48 Awọn ọkunrin Israeli si pada tọ̀ awọn ọmọ Benjamini, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu, ati ẹran, ati ohun gbogbo ti nwọn ní: gbogbo ilu ti nwọn ri ni nwọn fi iná kun pẹlu.

Onidajọ 21

Àwọn Ẹ̀yà Bẹnjamini Fẹ́ Iyawo

1 AWỌN ọkunrin Israeli si ti bura ni Mispe, pe, Ẹnikan ninu wa ki yio fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Benjamini li aya. 2 Awọn enia na si wá si Beti-eli, nwọn si joko nibẹ̀ titi di aṣalẹ niwaju Ọlọrun, nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun gidigidi. 3 Nwọn si wipe, OLUWA, Ọlọrun Israeli, ẽṣe ti o fi ri bayi ni Israeli, ti ẹ̀ya kan fi bùku li oni ninu awọn enia Israeli? 4 O si ṣe ni ijọ́ keji, awọn enia na dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si mọ pẹpẹ kan nibẹ̀, nwọn si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. 5 Awọn ọmọ Israeli si wipe, Tali o wà ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli ti kò bá ijọ gòke tọ̀ OLUWA wá? Nitoripe nwọn ti bura nla niti ẹniti kò ba tọ̀ OLUWA wá ni Mispe, wipe, Pipa li a o pa a. 6 Awọn ọmọ Israeli si kãnu nitori Benjamini arakunrin wọn, nwọn si wipe, A ke ẹ̀ya kan kuro ni Israeli li oni. 7 Awa o ha ti ṣe niti obinrin fun awọn ti o kù, awa sá ti fi OLUWA bura pe, awa ki yio fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn li aya. 8 Nwọn si wipe, Ewo ni ninu awọn ẹ̀ya Israeli ti kò tọ̀ OLUWA wá ni Mispe? Si kiyesi i, kò sí ẹnikan ni ibudó ti o ti Jabeṣi-gileadi wá si ijọ. 9 Nitori nigbati a kà awọn enia na, si kiyesi i, kò sí ẹnikan nibẹ̀ ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi. 10 Ijọ si rán ẹgbã mẹfa ọkunrin ninu awọn akọni sibẹ̀, nwọn si fi aṣẹ fun wọn pe, Ẹ lọ ẹ si fi oju idà kọlù awọn ara Jabeṣi-gileadi, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọ wẹrẹ. 11 Eyiyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: gbogbo ọkunrin, ati gbogbo obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin li ẹnyin o parun patapata. 12 Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani. 13 Gbogbo ijọ si ranṣẹ lọ bá awọn ọmọ Benjamini ti o wà ninu okuta Rimmoni sọ̀rọ, nwọn si fi alafia lọ̀ wọn. 14 Benjamini si pada li akokò na; nwọn si fun wọn li obinrin ti nwọn dasi ninu awọn obinrin Jabeṣi-gileadi: ṣugbọn sibẹ̀ nwọn kò si kari wọn. 15 Awọn enia na si kãnu nitori Benjamini, nitoripe OLUWA ṣe àlàfo ninu awọn ẹ̀ya Israeli. 16 Nigbana li awọn àgba ijọ wipe, Kini awa o ṣe niti obinrin fun awọn iyokù, nitoripe a ti pa gbogbo awọn obinrin run kuro ni Benjamini? 17 Nwọn si wipe, Ilẹ-iní kan yio wà fun awọn ti o ti sálà ni Benjamini, ki ẹ̀ya kan ki o má ba parun kuro ni Israeli. 18 Ṣugbọn awa kò lè fi aya fun wọn ninu awọn ọmọbinrin wa: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti bura, wipe, Egún ni fun ẹniti o ba fi aya fun Benjamini. 19 Nwọn si wipe, Kiyesi i, ajọ OLUWA wà li ọdọdún ni Ṣilo ni ìha ariwa Beti-eli, ni ìha ìla-õrùn ti opópo ti o lọ soke lati Beti-eli lọ titi dé Ṣekemu, ati ni ìha gusù ti Lebona. 20 Nwọn si fi aṣẹ fun awọn ọmọ Benjamini wipe, Ẹ lọ ki ẹ si ba sinu ọgbà-àjara; 21 Ki ẹ si wò, si kiyesi i, bi awọn ọmọbinrin Ṣilo ba jade wá lati jó ninu ijó wọnni, nigbana ni ki ẹnyin ki o jade lati inu ọgbà-àjara wá, ki olukuluku ọkunrin nyin ki o si mú aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Ṣilo, ki ẹnyin ki o si lọ si ilẹ Benjamini. 22 Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi. 23 Awọn ọmọ Benjamini si ṣe bẹ̃, nwọn si mú aya, gẹgẹ bi iye wọn, ninu awọn ẹniti njó, awọn ti nwọn múlọ; nwọn si lọ nwọn pada si ilẹ-iní wọn nwọn si kọ ilu wọnni, nwọn si joko sinu wọn. 24 Nigbana li awọn ọmọ Israeli si lọ lati ibẹ̀, olukuluku enia si ẹ̀ya tirẹ̀, ati si idile tirẹ̀, nwọn si jade lati ibẹ̀ lọ olukuluku enia si ilẹ-iní tirẹ̀. 25 Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.

Rutu 1

Elimeleki ati Idile rẹ̀ lọ lati máa gbe ni Moabu

1 O si ṣe li ọjọ́ wọnni ti awọn onidajọ nṣe olori, ìyan kan si mu ni ilẹ na. ọkunrin kan lati Betilehemu-juda si lọ ṣe atipo ni ilẹ Moabu, on, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin meji. 2 Orukọ ọkunrin na a si ma jẹ́ Elimeleki, orukọ obinrin rẹ̀ a si ma jẹ́ Naomi, orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji a si ma jẹ́ Maloni ati Kilioni, awọn ara Efrata ti Betilehemu-juda. Nwọn si wá si ilẹ Moabu, nwọn si ngbé ibẹ̀. 3 Elimeleki ọkọ Naomi si kú; o si kù on, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji. 4 Nwọn si fẹ́ aya ninu awọn obinrin Moabu; orukọ ọkan a ma jẹ́ Orpa, orukọ ekeji a si ma jẹ́ Rutu: nwọn si wà nibẹ̀ nìwọn ọdún mẹwa. 5 Awọn mejeji, Maloni ati Kilioni, si kú pẹlu; obinrin na li o si kù ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji ati ọkọ rẹ̀.

Náómì àti Rutu Padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

6 Nigbana li o dide pẹlu awọn aya-ọmọ rẹ̀, ki o le pada lati ilẹ Moabu wá: nitoripe o ti gbọ́ ni ilẹ Moabu bi OLUWA ti bẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò ni fifi onjẹ fun wọn. 7 O si jade kuro ni ibi ti o gbé ti wà, ati awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nwọn si mu ọ̀na pọ̀n lati pada wá si ilẹ Juda. 8 Naomi si wi fun awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pe, Ẹ lọ, ki olukuluku pada lọ si ile iya rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe rere fun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti ṣe fun awọn okú, ati fun mi. 9 Ki OLUWA ki o fi fun nyin ki ẹnyin le ri isimi, olukuluku nyin ni ile ọkọ rẹ̀. Nigbana li o fi ẹnu kò wọn lẹnu; nwọn si gbé ohùn wọn soke nwọn si sọkun. 10 Nwọn si wi fun u pe, Nitõtọ awa o bá ọ pada lọ sọdọ awọn enia rẹ. 11 Naomi si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin mi ẹ pada: ẽṣe ti ẹnyin o fi bá mi lọ? mo ha tun ní ọmọkunrin ni inu mi, ti nwọn iba fi ṣe ọkọ nyin? 12 Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin; 13 Ẹnyin ha le duro dè wọn titi nwọn o fi dàgba? Ẹnyin o le duro dè wọn li ainí ọkọ? Rara o, ẹnyin ọmọbinrin mi; nitoripe inu mi bàjẹ́ gidigidi nitori nyin, ti ọwọ́ OLUWA fi jade si mi. 14 Nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si tun sọkun: Orpa si fi ẹnu kò iya-ọkọ rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn Rutu fàmọ́ ọ. 15 On si wipe, Kiyesi i, orogun rẹ pada sọdọ awọn enia rẹ̀, ati sọdọ oriṣa rẹ̀: iwọ pada tẹlé orogun rẹ. 16 Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi: 17 Ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibẹ̀ li a o si sin mi: ki OLUWA ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi ohun kan bikoṣe ikú ba yà iwọ ati emi. 18 Nigbati on ri pe o ti pinnu rẹ̀ tán lati bá on lọ, nigbana li o dẹkun ọ̀rọ ibá a sọ. 19 Bẹ̃ni awọn mejeji lọ titi nwọn fi dé Betilehemu. O si ṣe, ti nwọn dé Betilehemu, gbogbo ilu si dide nitori wọn, nwọn si wipe, Naomi li eyi? 20 On si wi fun wọn pe, Ẹ má pè mi ni Naomi mọ́, ẹ mã pè mi ni Mara: nitoriti Olodumare hùwa kikorò si mi gidigidi. 21 Mo jade lọ ni kikún, OLUWA si tun mú mi pada bọ̀wá ile li ofo: ẽhaṣe ti ẹnyin fi npè mi ni Naomi, nigbati OLUWA ti jẹritì mi, Olodumare si ti pọn mi loju? 22 Bẹ̃ni Naomi padawá, ati Rutu ara Moabu, aya-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹniti o ti ilẹ Moabu wá; nwọn si wá si Beti-lehemu ni ìbẹrẹ ikore ọkà-barle.

Rutu 2

Rutu Ṣiṣẹ́ ninu Oko Boasi

1 NAOMI si ní ibatan ọkọ rẹ̀ kan, ọlọrọ̀ pupọ̀, ni idile Elimeleki; orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Boasi. 2 Rutu ara Moabu si wi fun Naomi pe, Jẹ ki emi lọ si oko nisisiyi, ki emi si ma peṣẹ́-ọkà lẹhin ẹniti emi o ri õre-ọfẹ́ li oju rẹ̀. On si wipe, Lọ, ọmọbinrin mi. 3 On si lọ, o si dé oko, o si peṣẹ́-ọkà lẹhin awọn olukore: o si wa jẹ pe apa oko ti o bọ si jẹ́ ti Boasi, ti iṣe ibatan Elimeleki. 4 Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ. 5 Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi? 6 Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa. 7 O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile. 8 Nigbana ni Boasi wi fun Rutu pe, Iwọ kò gbọ́, ọmọbinrin mi? Máṣe lọ peṣẹ́-ọkà li oko miran, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe re ihin kọja, ṣugbọn ki o faramọ́ awọn ọmọbinrin mi nihin. 9 Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn. 10 Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi? 11 Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí. 12 Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle. 13 Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin. 14 Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ. 15 Nigbati o si dide lati peṣẹ́-ọkà, Boasi si paṣẹ fun awọn ọmọkunrin rẹ̀, wipe, Ẹ jẹ ki o peṣẹ́-ọkà ani ninu awọn ití, ẹ má si ṣe bá a wi. 16 Ki ẹ si yọ diẹ ninu ití fun u, ki ẹ si fi i silẹ, ki ẹ si jẹ ki o ṣà a, ẹ má si ṣe bá a wi. 17 Bẹ̃li o peṣẹ́-ọkà li oko titi o fi di aṣalẹ, o si gún eyiti o kójọ, o si to bi òṣuwọn efa ọkà-barle kan. 18 O si gbé e, o si lọ si ilu: iya-ọkọ rẹ̀ si ri ẽṣẹ́ ti o pa: on si mú jade ninu eyiti o kù lẹhin ti o yó, o si fi fun u. 19 Iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ gbé peṣẹ́ li oni? nibo ni iwọ si ṣiṣẹ? ibukún ni fun ẹniti o fiyesi ọ. O si sọ ọdọ ẹniti on ṣiṣẹ fun iya-ọkọ rẹ̀, o si wipe, Boasi li orukọ ọkunrin ti mo ṣiṣẹ lọdọ rẹ̀ li oni. 20 Naomi si wi fun aya-ọmọ rẹ̀ pe, Ibukún ni fun u lati ọdọ OLUWA wá, ẹniti kò dẹkun ore rẹ̀ lati ṣe fun awọn alãye, ati fun awọn okú. Naomi si wi fun u pe, ọkunrin na sunmọ wa, ibatan ti o sunmọ wa ni. 21 Rutu obinrin Moabu na si wipe, O wi fun mi pẹlu pe, Ki iwọ ki o faramọ́ awọn ọdọmọkunrin mi, titi nwọn o fi pari gbogbo ikore mi. 22 Naomi si wi fun Rutu aya-ọmọ rẹ̀ pe, O dara, ọmọbinrin mi, ki iwọ ki o ma bá awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe bá ọ pade li oko miran. 23 Bẹ̃li o faramọ́ awọn ọmọbinrin ọdọ Boasi lati ma peṣẹ́-ọkà titi ipari ikore ọkà-barle ati ti alikama; o si wà lọdọ iya-ọkọ rẹ̀.

Rutu 3

Rutu rí ọkọ fẹ́

1 NAOMI iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ọmọbinrin mi, emi ki yio ha wá ibi isimi fun ọ, ki o le dara fun ọ? 2 Njẹ nisisiyi ibatan wa ki Boasi iṣe, ọmọbinrin ọdọ ẹniti iwọ ti mbá gbé? Kiyesi i, o nfẹ ọkà-barle li alẹ yi ni ilẹ-ipakà rẹ̀. 3 Nitorina wẹ̀, ki o si para, ki o si wọ̀ aṣọ rẹ, ki o si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà: ṣugbọn má ṣe jẹ ki ọkunrin na ki o ri ọ titi on o fi jẹ ti on o si mu tán. 4 Yio si ṣe, nigbati o ba dubulẹ, ki iwọ ki o kiyesi ibi ti on o sùn si, ki iwọ ki o wọle, ki o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, ki o si dubulẹ; on o si sọ ohun ti iwọ o ṣe fun ọ. 5 O si wi fun u pe, Gbogbo eyiti iwọ wi fun mi li emi o ṣe. 6 O si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà na, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iya-ọkọ rẹ̀ palaṣẹ fun u. 7 Nigbati Boasi si jẹ ti o si mu tán, ti inu rẹ̀ si dùn, o lọ dubulẹ ni ikangun ikójọ ọkà: on si wá jẹjẹ, o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dubulẹ. 8 O si ṣe lãrin ọganjọ ẹ̀ru bà ọkunrin na, o si yi ara pada: si kiyesi i, obinrin kan dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀. 9 O si wipe, Iwọ tani? On si dahùn wipe, Emi Rutu ọmọbinrin ọdọ rẹ ni: nitorina nà eti-aṣọ rẹ bò ọmọbinrin ọdọ rẹ; nitori iwọ ni ibatan ti o sunmọ wa. 10 On si wipe, Alabukun ni iwọ lati ọdọ OLUWA wá, ọmọbinrin mi: nitoriti iwọ ṣe ore ikẹhin yi jù ti iṣaju lọ, niwọnbi iwọ kò ti tẹle awọn ọmọkunrin lẹhin, iba ṣe talakà tabi ọlọrọ̀. 11 Njẹ nisisiyi, ọmọbinrin mi máṣe bẹ̀ru; gbogbo eyiti iwọ wi li emi o ṣe fun ọ: nitori gbogbo agbajọ awọn enia mi li o mọ̀ pe obinrin rere ni iwọ iṣe. 12 Njẹ nisisiyi ibatan ti o sunmọ nyin li emi iṣe nitõtọ: ṣugbọn ibatan kan wà ti o sunmọ nyin jù mi lọ. 13 Duro li oru yi, yio si ṣe li owurọ̀, bi on o ba ṣe iṣe ibatan si ọ, gẹgẹ; jẹ ki o ṣe iṣe ibatan: ṣugbọn bi kò ba fẹ́ ṣe iṣe ibatan si ọ, nigbana ni emi o ṣe iṣe ibatan si ọ, bi OLUWA ti wà: dubulẹ titi di owurọ̀. 14 On si dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀ titi di owurọ̀: o si dide ki ẹnikan ki o to mọ̀ ẹnikeji. On si wipe, Má ṣe jẹ ki a mọ̀ pe obinrin kan wá si ilẹ-ipakà. 15 O si wipe, Mú aṣọ-ileke ti mbẹ lara rẹ wá, ki o si dì i mú: nigbati o si dì i mú, o wọ̀n òṣuwọn ọkà-barle mẹfa, o si gbé e rù u: on si wọ̀ ilu lọ. 16 Nigbati o si dé ọdọ iya-ọkọ rẹ̀, on wipe, Iwọ tani nì ọmọbinrin mi? O si wi gbogbo eyiti ọkunrin na ṣe fun on fun u. 17 O si wipe, Òṣuwọn ọkà-barle mẹfa wọnyi li o fi fun mi; nitori o wi fun mi pe, Máṣe ṣanwọ tọ̀ iya-ọkọ rẹ lọ. 18 Nigbana li on wipe, Joko jẹ, ọmọbinrin mi, titi iwọ o fi mọ̀ bi ọ̀ran na yio ti jasi: nitoripe ọkunrin na ki yio simi, titi yio fi pari ọ̀ran na li oni.

Rutu 4

Boasi Ṣú Rutu Lópó

1 NIGBANA ni Boasi lọ si ẹnu-bode, o si joko nibẹ̀: si kiyesi i, ibatan na ẹniti Boasi sọ̀rọ rẹ̀ nkọja; o si pe, Iwọ alamọrin! yà, ki o si joko nihin. O si yà, o si joko. 2 O si mú ọkunrin mẹwa ninu awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ joko nihin. Nwọn si joko. 3 O si wi fun ibatan na pe, Naomi, ẹniti o ti ilẹ Moabu pada wa, o ntà ilẹ kan, ti iṣe ti Elimeleki arakunrin wa: 4 Mo si rò lati ṣí ọ leti rẹ̀, wipe, Rà a niwaju awọn ti o joko nihin, ati niwaju awọn àlagba awọn enia mi. Bi iwọ o ba rà a silẹ, rà a silẹ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rà a silẹ, njẹ wi fun mi, ki emi ki o le mọ̀: nitoriti kò sí ẹnikan lati rà a silẹ lẹhin rẹ; emi li o si tẹle ọ. On si wipe, Emi o rà a silẹ. 5 Nigbana ni Boasi wipe, Li ọjọ́ ti iwọ ba rà ilẹ na li ọwọ́ Naomi, iwọ kò le ṣe àirà a li ọwọ́ Rutu ara Moabu pẹlu, aya ẹniti o kú, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀. 6 Ibatan na si wipe, Emi kò le rà a silẹ fun ara mi, ki emi má ba bà ilẹ-iní mi jẹ́: iwọ rà eyiti emi iba rà silẹ; nitori emi kò le rà a. 7 Iṣe wọn nigbãni ni Israeli niti ìrasilẹ, ati niti iparọ si li eyi, lati fi idí ohun gbogbo mulẹ, ẹnikini a bọ́ bàta rẹ̀, a si fi i fun ẹnikeji rẹ̀: ẹrí li eyi ni Israeli, 8 Bẹ̃ni ibatan na wi fun Boasi pe, Rà a fun ara rẹ. O si bọ́ bàta rẹ̀. 9 Boasi si wi fun awọn àgbagba, ati fun gbogbo awọn enia pe, Ẹnyin li elẹri li oni, pe mo rà gbogbo nkan ti iṣe ti Elimeleki, ati gbogbo nkan ti iṣe ti Kilioni, ati ti Maloni, li ọwọ́ Naomi. 10 Pẹlupẹlu Rutu ara Moabu, aya Maloni ni mo rà li aya mi, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀, ki orukọ okú ki o má ba run ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati li ẹnu-bode ilu rẹ̀: ẹnyin li ẹlẹri li oni. 11 Gbogbo awọn enia ti o wà li ẹnu-bode, ati awọn àgbagba, si wipe, Awa ṣe ẹlẹri. Ki OLUWA ki o ṣe obinrin na ti o wọ̀ ile rẹ bi Rakeli ati bi Lea, awọn meji ti o kọ ile Israeli: ki iwọ ki o si jasi ọlọlá ni Efrata, ki o si jasi olokikí ni Betilehemu. 12 Ki ile rẹ ki o si dabi ile Peresi, ẹniti Tamari bi fun Juda, nipa irú-ọmọ ti OLUWA yio fun ọ lati ọdọ ọmọbinrin yi.

Boasi ati Ìrandíran Rẹ̀

13 Boasi si mú Rutu, on si di aya rẹ̀; nigbati o si wọle tọ̀ ọ, OLUWA si mu ki o lóyun, o si bi ọmọkunrin kan. 14 Awọn obinrin si wi fun Naomi pe, Olubukun li OLUWA, ti kò fi ọ silẹ li ainí ibatan li oni, ki o si jẹ́ olokikí ni Israeli. 15 On o si jẹ́ olumupada ẹmi rẹ, ati olutọju ogbó rẹ: nitori aya-ọmọ rẹ, ẹniti o fẹ́ ọ, ti o san fun ọ jù ọmọkunrin meje lọ, li o bi i. 16 Naomi si gbé ọmọ na, o si tẹ́ ẹ si owókan-àiya rẹ̀, o si di alagbatọ́ rẹ̀. 17 Awọn obinrin aladugbo rẹ̀ si sọ ọ li orukọ, wipe, A bi ọmọkunrin kan fun Naomi; nwọn si pè orukọ rẹ̀ ni Obedi: on ni baba Jesse, baba Dafidi. 18 Wọnyi ni iran Peresi: Peresi bi Hesroni; 19 Hesroni si bi Ramu, Ramu si bi Amminadabu; 20 Amminadabu si bi Naṣoni, Naṣoni si bi Salmoni; 21 Salmoni si bi Boasi, Boasi si bi Obedi; 22 Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Dafidi.

1 Samueli 1

Ẹlkana ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ìlú Ṣilo

1 NIGBANA ọkunrin kan wà, ara Ramataim-sofimu, li oke Efraimu, orukọ rẹ̀ ama jẹ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ara Efrata. 2 O si ni aya meji; orukọ ekini ama jẹ Hanna, orukọ ekeji a si ma jẹ Peninna: Peninna si bimọ, ṣugbọn Hanna kò bi. 3 Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọdun lati sìn ati lati ṣe irubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ọmọ Eli mejeji Hofni ati Finehasi alufa Oluwa, si wà nibẹ. 4 Nigbati o si di akoko ti Elkana ṣe irubọ, o fi ipin fun Peninna aya rẹ̀, ati fun gbogbo ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin. 5 Ṣugbọn Hanna li on fi ipin ẹni meji fun; nitori ti o fẹ Hanna: ṣugbọn Oluwa ti se e ni inu. 6 Orogún rẹ̀ pẹlu a si ma tọ́ ọ gidigidi lati mu u binu, nitoriti Oluwa ti se e ni inu. 7 Bi on iti ma ṣe bẹ̃ lọdọdun, nigbati Hanna ba goke lọ si ile Oluwa, bẹni Peninna ima bà a ni inu jẹ; nitorina ama sọkun, kò si jẹun. 8 Nigbana ni Elkana ọkọ rẹ̀ si sọ fun u pe, Hanna, ẽṣe ti iwọ nsọkun? ẽṣe ti iwọ kò si jẹun? ẽsi ti ṣe ti inu rẹ fi bajẹ? emi ko ha sàn fun ọ ju ọmọ mẹwa lọ bi?

Hana ati Eli

9 Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa. 10 On si wà ninu ibinujẹ ọkàn, o si mbẹ Oluwa, o si sọkun gidigidi. 11 On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori. 12 O si ṣe bi o ti mbẹbẹ sibẹ niwaju Oluwa, bẹ̃ni Eli kiyesi ẹnu rẹ̀. 13 Njẹ Hanna, on nsọ̀rọ li ọkàn rẹ̀; kiki etè rẹ̀ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ́ ohùn rẹ̀: nitorina ni Eli fi rò pe, o mu ọti-waini yó. 14 Eli si wi fun u pe, Iwọ o ti mu ọti-waini pẹ to? mu ọti-waini rẹ kuro lọdọ rẹ. 15 Hanna si dahun wipe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, emi li obinrin oniròbinujẹ ọkàn: emi kò mu ọti-waini tabi ọti lile, ṣugbọn ọkàn mi li emi ntú jade niwaju Oluwa. 16 Má ṣe ka iranṣẹbinrin rẹ si ọmọbinrin Beliali: nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ irò ati ibinujẹ inu mi ni mo ti nsọ disisiyi. 17 Nigbana ni Eli dahun o si wipe, Ma lọ li alafia: ki Ọlọrun Israeli ki o fi idahun ibere ti iwọ bere lọdọ rẹ̀ fun ọ. 18 On si wipe, Ki iranṣẹbinrin rẹ ki o ri ore-ọfẹ loju rẹ. Bẹ̃li obinrin na ba tirẹ̀ lọ, o si jẹun, ko si fà oju ro mọ.

Ìbí Samuẹli ati Ìyàsímímọ́ Rẹ̀

19 Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn wolẹ sìn niwaju Oluwa, nwọn pada wá si ile wọn si Rama: Elkana si mọ aya rẹ̀; Oluwa si ranti rẹ̀. 20 Nitorina, o si ṣe, nigbati ọjọ rẹ̀ pe lẹhin igbati Hanna loyun, o si bi ọmọkunrin kan, o si pe orukọ rẹ̀ ni Samueli, pe, Nitoriti mo bere rẹ̀ lọwọ Oluwa. 21 Ọkunrin na Elkana, ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀, goke lọ lati rubọ ọdun si Oluwa, ati lati san ileri ifẹ rẹ̀. 22 Ṣugbọn Hanna ko goke lọ; nitori ti o wi fun ọkọ rẹ̀ pe, o di igbati mo ba gba ọmu lẹnu ọmọ na, nigbana li emi o mu u lọ, ki on ki o le fi ara han niwaju Oluwa, ki o si ma gbe ibẹ titi lai. 23 Elkana ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ṣe eyi ti o tọ li oju rẹ; duro titi iwọ o fi gba ọmu li ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ki Oluwa ki o sa mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ. Bẹ̃li obinrin na si joko, o si fi ọmu fun ọmọ rẹ̀ titi o fi gbà a lẹnu rẹ̀. 24 Nigbati o si gba ọmu li ẹnu rẹ̀, o si mu u goke lọ pẹlu ara rẹ̀, pẹlu ẹgbọrọ malu mẹta, ati iyẹfun efa kan, ati igo ọti-wain kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọmọde. 25 Nwọn pa ẹgbọrọ malu, nwọn si mu ọmọ na tọ̀ Eli wá. 26 Hanna si wipe, oluwa mi, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, oluwa mi, emi li obinrin na ti o duro li ẹba ọdọ rẹ nihin ti ntọrọ lọdọ Oluwa. 27 Ọmọ yi ni mo ntọrọ; Oluwa si fi idahun ibere ti mo bere lọdọ rẹ̀ fun mi: 28 Nitorina pẹlu emi fi i fun Oluwa; ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀: nitoriti mo ti bere rẹ̀ fun Oluwa. Nwọn si wolẹ-sin Oluwa nibẹ.

1 Samueli 2

Adura Hana

1 HANNA si gbadura pe, Ọkàn mi yọ̀ si Oluwa, iwo mi li a si gbe soke si Oluwa: ẹnu mi si gboro lori awọn ọta mi; nitoriti emi yọ̀ ni igbala rẹ. 2 Kò si ẹniti o mọ́ bi Oluwa: kò si ẹlomiran boyẹ̀ ni iwọ; bẹ̃ni kò si apata bi Ọlọrun wa. 3 Máṣe halẹ; má jẹ ki igberaga ki o ti ẹnu nyin jade: nitoripe Ọlọrun olùmọ̀ ni Oluwa, lati ọdọ rẹ̀ wá li ati iwọ̀n ìwa. 4 Ọrun awọn alagbara ti ṣẹ, awọn ti o ṣe alailera li a fi agbara dì li amure. 5 Awọn ti o yo fun onjẹ ti fi ara wọn ṣe alagbaṣe: awọn ti ebi npa kò si ṣe alaini: tobẹ̃ ti àgan fi bi meje: ẹniti o bimọ pipọ si di alailagbara. 6 Oluwa pa, o si sọ di ayè: o mu sọkalẹ lọ si ibojì, o si gbe soke. 7 Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbe soke. 8 O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn. 9 Yio pa ẹṣẹ awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ, awọn enia buburu ni yio dakẹ li okunkun; nipa agbara kò si ọkunrin ti yio bori. 10 Ao fọ́ awọn ọta Oluwa tutu; lati ọrun wá ni yio san ãrá si wọn: Oluwa yio ṣe idajọ opin aiye; yio fi agbara fun ọba rẹ̀, yio si gbe iwo ẹni-amì-ororo rẹ̀ soke. 11 Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa.

Àwọn Ọmọ Eli

12 Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ Oluwa. 13 Iṣe awọn alufa pẹlu awọn enia ni, nigbati ẹnikan ba ṣe irubọ, iranṣẹ alufa a de, nigbati ẹran na nho lori iná, ti on ti ọpa-ẹran oniga mẹta li ọwọ́ rẹ̀. 14 On a si fi gun inu apẹ, tabi kẹtili tabi òdu, tabi ikokò, gbogbo eyi ti ọpa-ẹran oniga na ba mu wá oke, alufa a mu u fun ara rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn nṣe si gbogbo Israeli ti o wá si ibẹ̀ ni Ṣilo. 15 Pẹlu ki nwọn ki o to sun ọra na, iranṣẹ alufa a de, a si wi fun ọkunrin ti on ṣe irubọ pe, Fi ẹran fun mi lati sun fun alufa; nitoriti kì yio gba ẹran sisè lọwọ rẹ, bikoṣe tutù. 16 Ọkunrin na si wi fun u pe, Jẹ ki wọn sun ọra na nisisiyi, ki o si mu iyekiye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana li o da a lohun pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ki iwọ ki o fi i fun mi nisisiyi: bikoṣe bẹ̃, emi o fi agbara gbà a. 17 Ẹṣẹ awọn ọdọmọkunrin na si tobi gidigidi niwaju Oluwa: nitoriti enia korira ẹbọ Oluwa.

Samuẹli ní Ṣilo

18 Ṣugbọn Samueli nṣe iranṣẹ niwaju Oluwa, o ṣe ọmọde, ti a wọ̀ ni efodi ọgbọ. 19 Pẹlupẹlu iya rẹ̀ da aṣọ ileke penpe fun u, a ma mu fun u wá lọdọdun, nigbati o ba bá ọkọ rẹ̀ goke wá lati ṣe irubọ ọdun. 20 Eli sure fun Elkana ati aya rẹ̀ pe ki Oluwa ki o ti ara obinrin yi fun ọ ni iru-ọmọ nipa ibere na ti o bere lọdọ Oluwa. Nwọn si lọ si ile wọn. 21 Oluwa si boju wo Hanna, o si loyun, o bi ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin meji. Samueli ọmọ na si ndagbà niwaju Oluwa.

Eli ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

22 Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ. 23 O si wi fun wọn pe, Etiri ti emi fi ngbọ́ iru nkan bẹ̃ si nyin? nitoriti emi ngbọ́ iṣe buburu nyin lati ọdọ gbogbo enia yi wá. 24 Bẹ̃kọ, ẹnyin ọmọ mi, nitori ki iṣe ihinrere li emi gbọ́: ẹnyin mu enia Ọlọrun dẹṣẹ̀. 25 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn. 26 Ọmọ na Samueli ndagba, o si ri ojurere lọdọ Oluwa, ati enia pẹlu.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìdílé Eli

27 Ẹni Ọlọrun kan tọ Eli wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Gbangba ki emi fi ara hàn ile baba rẹ, nigbati nwọn mbẹ ni Egipti ninu ile Farao? 28 Emi ko si yàn a kuro larin gbogbo ẹya Israeli lati jẹ alufa mi, lati rubọ lori pẹpẹ mi, lati fi turari jona, lati wọ efodi niwaju mi, emi si fi gbogbo ẹbọ ti ọmọ Israeli ima fi iná sun fun idile baba rẹ? 29 Eṣe ti ẹnyin fi tapa si ẹbọ ati ọrẹ mi, ti mo pa li aṣẹ ni ibujoko mi: iwọ si bu ọla fun awọn ọmọ rẹ jù mi lọ, ti ẹ si fi gbogbo ãyo ẹbọ Israeli awọn enia mi mu ara nyin sanra? 30 Nitorina Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti wi nitotọ pe, ile rẹ ati ile baba rẹ, yio ma rin niwaju mi titi: ṣugbọn nisisiyi Oluwa wipe, ki a má ri i; awọn ti o bu ọla fun mi li emi o bu ọla fun, ati awọn ti kò kà mi si li a o si ṣe alaikasi. 31 Kiye si i, ọjọ wọnni mbọ̀, ti emi o ke iru rẹ kurò, ati iru baba rẹ, kì yio si arugbo kan ninu ile rẹ. 32 Iwọ o ri wahala ti Agọ, ninu gbogbo ọlà ti Ọlọrun yio fi fun Israeli: kì yio si si arugbo kan ninu ile rẹ lailai. 33 Ọkunrin ti iṣe tirẹ, ẹniti emi kì yio ke kuro ni ibi pẹpẹ mi, yio wà lati ma pọn ọ loju, lati ma bà ọ ninu jẹ; gbogbo iru ọmọ ile rẹ ni yio kú li abọ̀ ọjọ wọn. 34 Eyi li o jẹ àmi fun ọ, ti yio wá si ori ọmọ rẹ mejeji, si ori Hofni ati Finehasi, ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú. 35 Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo. 36 Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o ba kù ni ile rẹ yio wá tẹriba fun u nitori fadaka diẹ, ati nitori okele onjẹ, yio si wipe, Jọwọ fi mi sinu ọkan ninu iṣẹ awọn alufa, ki emi ki o le ma ri akara diẹ jẹ.

1 Samueli 3

OLUWA fara han Samuẹli

1 ỌMỌ na Samueli nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli. Ọ̀rọ Oluwa si ṣọwọ́n lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ̀. 2 O si ṣe li akoko na, Eli si dubulẹ ni ipo tirẹ̀, oju rẹ̀ bẹrẹ̀ si ṣõkun, tobẹ̃ ti ko le riran. 3 Ki itana Ọlọrun to kú ninu tempeli Oluwa, Samueli dubulẹ nibiti apoti Ọlọrun gbe wà, 4 Oluwa pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ. 5 O si sare tọ Eli, o si wipe, Emi nĩ; nitori ti iwọ pè mi. On wipe, emi kò pè: pada lọ dubulẹ. O si lọ dubulẹ. 6 Oluwa si tun npè, Samueli. Samueli si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitoriti iwọ pè mi. O si da a lohun, emi kò pè, ọmọ mi; padà lọ dubulẹ. 7 Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a. 8 Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na. 9 Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀. 10 Oluwa wá, o si duro, o si pè bi igbá ti o kọja, Samueli, Samueli. Nigbana ni Samueli dahun pè, Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ́. 11 Oluwa si wi fun Samueli pe, Kiyesi i, emi o ṣe ohun kan ni Israeli, eyi ti yio mu eti mejeji olukuluku awọn ti o gbọ́ ọ ho. 12 Li ọjọ na li emi o mu gbogbo ohun ti mo ti sọ si ile Eli ṣẹ: nigbati mo ba bẹrẹ, emi o si ṣe e de opin. 13 Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun. 14 Nitorina emi ti bura si ile Eli, pe ìwa-buburu ile Eli li a kì yio fi ẹbọ tabi ọrẹ wẹ̀nù lailai. 15 Samueli dubulẹ titi di owurọ, o si ṣi ilẹkun ile OLUWA. Samueli si bẹru lati rò ifihan na fun Eli. 16 Nigbana ni Eli pe Samueli, o si wipe, Samueli, ọmọ mi. On si dahun pe, Emi nĩ. 17 O si wipe, Kili ohun na ti Oluwa sọ fun ọ? emi bẹ ọ máṣe pa a mọ fun mi: ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si ọ, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ ba pa ohun kan mọ fun mi ninu gbogbo ohun ti o sọ fun ọ. 18 Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀. 19 Samueli ndagba, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀, kò si jẹ ki ọkan ninu ọ̀rọ rẹ̀ wọnni bọ́ silẹ. 20 Gbogbo Israeli lati Dani titi o fi de Beerṣeba mọ̀ pe a ti fi Samueli kalẹ ni woli fun Oluwa. 21 Oluwa si nfi ara hàn a ni Ṣilo: nitoriti Oluwa ti fi ara rẹ̀ han fun Samueli ni Ṣilo nipa ọ̀rọ Oluwa.

1 Samueli 4

Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn Ọmọ Israẹli

1 Ọ̀RỌ Samueli si wá si gbogbo Israeli: Israeli si jade lọ pade awọn Filistini lati jagun, nwọn do si eti Ebeneseri: awọn Filistini si do ni Afeki. 2 Awọn Filistini si tẹ itẹgun lati pade Israeli: nigbati nwọn pade ija, awọn Filistini si le Israeli: nwọn si pa iwọn ẹgbaji ọkunrin ni itẹgun ni papa. 3 Awọn enia si de budo, awọn agbà Israeli si wipe, Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini? Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni Ṣilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa. 4 Bẹli awọn enia si ranṣẹ si Ṣilo, pe ki nwọn gbe lati ibẹ wá apoti majẹmu Oluwa awọn ọmọ-ogun ẹniti o joko larin awọn kerubu: ati awọn ọmọ Eli mejeji, Hofni ati Finehasi, wà nibẹ pẹlu apoti majẹmu Ọlọrun. 5 Nigbati apoti majẹmu Oluwa de budo, gbogbo Israeli si ho yè, tobẹ̃ ti ilẹ mì. 6 Nigbati awọn Filistini si gbọ́ ohùn ariwo na, nwọn si wipe, Ohùn ariwo nla kili eyi ni budo awọn Heberu? O si wa ye wọn pe, apoti majẹmu Oluwa li o de budo. 7 Ẹ̀ru si ba awọn Filistini, nwọn si wipe, Ọlọrun wọ budo. Nwọn si wipe, Awa gbe! nitoripe iru nkan bayi kò si ri. 8 A gbe! tani yio gbà wa lọwọ Ọlọrun alagbara wọnyi? awọn wọnyi li Ọlọrun ti o fi gbogbo ipọnju pọn Egipti loju li aginju. 9 Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja. 10 Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun. 11 Nwọn si gbà apoti ẹri Ọlọrun: ọmọ Eli mejeji si kú, Hofni ati Finehasi.

Ikú Eli

12 Ọkunrin ara Benjamini kan sa lati ogun wá o si wá si Ṣilo lọjọ kanna, ti on ti aṣọ rẹ̀ fifaya, ati erupẹ lori rẹ̀. 13 Nigbati o si de, si wõ, Eli joko lori apoti kan lẹba ọ̀na o nṣọna: nitori aiyà rẹ̀ kò balẹ nitori apoti Ọlọrun. Ọkunrin na si wọ ilu lati rohin, gbogbo ilu fi igbe ta. 14 Eli si gbọ́ ohùn igbe na, o sì wipe, Ohùn igbe kili eyi? ọkunrin na si yara wá o si rò fun Eli. 15 Eli si di ẹni ejidilọgọrun ọdun; oju rẹ̀ di baibai, kò si le riran. 16 Ọkunrin na si wi fun Eli pe, Emi li ẹniti o ti ogun wá, loni ni mo sa ti ogun na wá; o si bi i pe, Eti ri, ọmọ mi? 17 Ẹniti o mu ihin wá si dahun o si wipe, Israeli sa niwaju awọn Filistini, iṣubu na si pọ ninu awọn enia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji, Hofni ati Finehasi si kú, nwọn si gbà apoti Ọlọrun. 18 O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun.

Ikú Opó Finehasi

19 Aya ọmọ rẹ̀, obinrin Finehasi, loyun, o si sunmọ ọjọ ibi rẹ̀; nigbati o si gbọ́ ihìn pe a ti gbà apoti Ọlọrun, ati pe, baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ kú, o kunlẹ, o si bimọ, nitori obí tẹ̀ ẹ. 20 Lakoko ikú rẹ̀ awọn obinrin ti o duro tì i si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; nitoriti iwọ bi ọmọkunrin kan. Ko dahun, kò si kà a si. 21 On si pe ọmọ na ni Ikabodu, wipe, Kò si ogo fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun, ati nitori ti baba ọkọ rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀. 22 O si wipe, Ogo kò si fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun.

1 Samueli 5

Àpótí Ẹ̀rí bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Filistia

1 AWỌN Filistini si gbe Apoti Ọlọrun, nwọn si mu u lati Ebeneseri wá si Aṣdodu. 2 Nigbati awọn Filistini gbe apoti Ọlọrun, nwọn si gbe e wá si ile Dagoni, nwọn gbe e kà ilẹ li ẹba Dagoni. 3 Nigbati awọn ara Aṣdodu ji li owurọ ọjọ keji, kiye si i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa. Nwọn si gbe Dagoni, nwọn si tun fi i si ipò rẹ̀. 4 Nigbati nwọn ji li owurọ̀ ọjọ keji, kiyesi i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa; ati ori Dagoni ati atẹlẹ ọwọ́ rẹ̀ mejeji ke kuro li oju ọ̀na; Dagoni ṣa li o kù fun ara rẹ̀. 5 Nitorina awọn alufa Dagoni, ati gbogbo awọn ti ima wá si ile Dagoni, kò si tẹ oju ọ̀na Dagoni ni Aṣdodu titi di oni. 6 Ọwọ́ Oluwa si wuwo si ara Aṣdodu, o si pa wọn run, o si fi iyọdi pọn wọn loju, ani Aṣdodu ati agbegbe rẹ̀. 7 Nigbati awọn enia Aṣdodu ri pe bẹ̃ li o ri, nwọn si wi pe, Apoti Ọlọrun Israeli kì yio ba wa gbe: nitoripe ọwọ́ rẹ̀ wuwo si wa, ati si Dagoni ọlọrun wa. 8 Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ. 9 O si ṣe pe, lẹhin igbati nwọn gbe e lọ tan, ọwọ́ Oluwa si wà si ilu na pẹlu iparun nla, o si pọn awọn enia ilu na loju, ati ọmọde ati agbà, nwọn ni iyọdi. 10 Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa. 11 Bẹ̃ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pe gbogbo ijoye Filistini jọ, nwọn si wipe, Rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, ki ẹ si jẹ ki o tun pada lọ si ipò rẹ̀, ki o má ba pa wa, ati awọn enia wa: nitoriti ipaiya ikú ti wà ni gbogbo ilu na; ọwọ́ Ọlọrun si wuwo gidigidi ni ibẹ. 12 Awọn ọmọkunrin ti kò kú ni a si fi iyọdi pọn loju: igbe ilu na si lọ soke ọrun.

1 Samueli 6

Wọ́n dá àpótí ẹ̀rí pada

1 APOTI Oluwa wà ni ilẹ awọn Filistini li oṣù meje. 2 Awọn Filistini si pe awọn alufa ati awọn alasọtẹlẹ, wipe, Awa o ti ṣe apoti Oluwa si? sọ fun wa ohun ti awa o fi rán a lọ si ipò rẹ̀. 3 Nwọn si wipe, Bi ẹnyin ba rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, máṣe rán a lọ lofo; ṣugbọn bi o ti wu ki o ri, ẹ ṣe irubọ ẹbi fun u; a o si mu nyin lara da, ẹnyin o si mọ̀ ohun ti o ṣe ti ọwọ́ rẹ̀ kò fi kuro li ara nyin. 4 Nwọn wipe, Kini irubọ na ti a o fi fun u? Nwọn si dahun pe, Iyọdi wura marun, ati ẹ̀liri wura marun, gẹgẹ bi iye ijoye Filistini: nitoripe ajakalẹ arùn kanna li o wà li ara gbogbo nyin, ati awọn ijoye nyin. 5 Nitorina ẹnyin o ya ere iyọdi nyin, ati ere ẹ̀liri nyin ti o bà ilẹ na jẹ; ẹnyin o si fi ogo fun Ọlọrun Israeli: bọya yio mu ọwọ́ rẹ̀ fẹrẹ lara nyin, ati lara awọn ọlọrun nyin, ati kuro lori ilẹ nyin, 6 Njẹ ẽtiṣe ti ẹnyin fi se aiya nyin le, bi awọn ara Egipti ati Farao ti se aiya wọn le? nigbati o ṣiṣẹ iyanu nla larin wọn, nwọn kò ha jẹ ki awọn enia na lọ bi? nwọn si lọ. 7 Nitorina ẹ ṣe kẹkẹ titun kan nisisiyi, ki ẹ si mu abo malu meji ti o nfi ọmu fun ọmọ, eyi ti kò ti igbà ajaga si ọrun ri, ki ẹ si so o mọ kẹkẹ́ na, ki ẹnyin ki o si mu ọmọ wọn kuro lọdọ wọn wá ile. 8 Ki ẹnyin ki o si gbe apoti Oluwa nì ka ori kẹkẹ̀ na, ki ẹnyin ki o si fi ohun elo wura wọnni ti ẹnyin dá fun u nitori ẹbọ ọrẹ irekọja, ninu apoti kan li apakan rẹ̀; ki ẹnyin rán a, yio si lọ. 9 Ki ẹ si kiyesi i, bi o ba lọ si ọ̀na agbegbe tirẹ̀ si Betṣemeṣi, a jẹ pe on na li o ṣe wa ni buburu yi: ṣugbọn bi kò ba ṣe bẹ̃, nigbana li awa o to mọ̀ pe, ki iṣe ọwọ́ rẹ̀ li o lù wa, ṣugbọn ẽṣi li o ṣe si wa. 10 Awọn ọkunrin na si ṣe bẹ̃: nwọn si mu abo malu meji; ti nfi ọmu fun ọmọ, nwọn si dè wọn mọ kẹkẹ́ na, nwọn si se ọmọ wọn mọ ile. 11 Nwọn gbe apoti Oluwa wa lori kẹkẹ́ na, apoti pẹlu ẹ̀liri wura na, ati ere iyọdí wọn. 12 Awọn abo malu na si lọ tàra si ọ̀na Betṣemeṣi, nwọn si nke bi nwọn ti nlọ li ọ̀na opopo, nwọn kò yà si ọtún tabi si osì; awọn ijoye Filistini tẹle wọn lọ si agbegbe Betṣemeṣi. 13 Awọn ara Betṣemeṣi nkore alikama wọn li afonifoji: nwọn gbe oju wọn soke, nwọn si ri apoti na, nwọn si yọ̀ lati ri i. 14 Kẹkẹ́ na si wọ inu oko Joṣua, ara Betṣemeṣi, o si duro nibẹ, ibi ti okuta nla kan gbe wà: nwọn la igi kẹkẹ na, nwọn si fi malu wọnni ru ẹbọ sisun si Oluwa. 15 Awọn ọmọ Lefi si sọ apoti Oluwa na kalẹ, ati apoti ti o wà pẹlu rẹ̀, nibiti ohun elo wura wọnni gbe wà, nwọn si fi le ori okuta nla na: awọn ọkunrin Betṣemeṣi si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ si Oluwa li ọjọ na. 16 Nigbati awọn ijoye Filistini marun si ri i, nwọn tun yipada lọ si Ekroni li ọjọ kanna, 17 Wọnyi ni iyọdi wura ti awọn Filistini dá fun irubọ si Oluwa; ọkan ti Aṣdodu, ọkan ti Gasa, ọkan ti Aṣkeloni, ọkan ti Gati, ọkan ti Ekroni. 18 Ẹliri wura na si ri gẹgẹ bi iye gbogbo ilu awọn Filistini ti o jasi ti awọn ijoye marun na, ati ilu, ati ilu olodi, ati awọn ileto, titi o fi de ibi okuta nla Abeli, lori eyi ti nwọn gbe apoti Oluwa kà: okuta eyiti o wà titi di oni ninu oko Joṣua ara Betṣemeṣi. 19 On si pọn awọn ọkunrin Betṣemeṣi loju, nitoriti nwọn bẹ inu apoti Oluwa wò, iye wọn ti o pa ninu awọn enia na jẹ ẹgbã mẹdọgbọn o le ãdọrin ọkunrin, awọn enia na pohunrere ẹkun nitoriti Oluwa fi iparun nla pa ọpọ̀ awọn enia na run.

Àpótí Ẹ̀rí ní Kiriati Jearimu

20 Awọn ọkunrin Betṣemeṣi si wipe, Tani yio le duro niwaju Oluwa Ọlọrun mimọ́ yi? ati lọdọ tani yio lọ bi o kuro lọdọ wa? 21 Nwọn ran awọn onṣẹ si awọn ara Kirjatjearimu wipe, Awọn Filistini mu apoti Oluwa wá; ẹ sọkalẹ wá, ki ẹ gbe e lọ sọdọ nyin.

1 Samueli 7

1 AWỌN ọkunrin Kirjatjearimu wá, nwọn gbe apoti Oluwa na, nwọn si mu u wá si ile Abinadabu ti o wà lori oke, nwọn si ya Eleasari ọmọ rẹ̀ si mimọ́ lati ma tọju apoti Oluwa. 2 O si ṣe, lati igba ti apoti Oluwa fi wà ni Kirjatjearimu, ọjọ na pẹ́; o si jẹ ogun ọdun: gbogbo ile Israeli si pohunrere ẹkun si Oluwa. 3 Samueli si sọ fun gbogbo ile Israeli, wipe, Bi ẹnyin ba fi gbogbo ọkàn nyin yipada si Oluwa, ẹ mu ajeji ọlọrun wọnni, ati Aṣtaroti kuro larin nyin, ki ẹnyin ki o si pese ọkàn nyin silẹ fun Oluwa, ki ẹ si ma sin on nikanṣoṣo: yio si gbà nyin lọwọ́ Filistini. 4 Awọn ọmọ Israeli si mu Baalimu ati Aṣtaroti kuro, nwọn si sìn Oluwa nikan. 5 Samueli si wipe, Pe gbogbo Israeli jọ si Mispe, emi o si bẹbẹ si Oluwa fun nyin, 6 Nwọn si pejọ si Mispe, nwọn pọn omi, nwọn si tú u silẹ niwaju Oluwa, nwọn gbawẹ li ọjọ na, nwọn si wi nibẹ pe, Awa ti dẹṣẹ si Oluwa. Samueli si ṣe idajọ awọn ọmọ Israeli ni Mispe. 7 Awọn Filistini si gbọ́ pe, awọn ọmọ Israeli pejọ si Mispe, awọn ijoye Filistini si goke tọ Israeli lọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, nwọn bẹ̀ru awọn Filistini. 8 Awọn ọmọ Israeli si wi fun Samueli pe, Máṣe dakẹ ati ma ke pe Oluwa Ọlọrun wa fun wa, yio si gbà wa lọwọ́ awọn Filistini. 9 Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ. 10 Bi Samueli ti nru ẹbọ sisun na lọwọ́, awọn Filistini si sunmọ Israeli lati ba wọn jà: ṣugbọn Oluwa sán ãrá nla li ọjọ na sori awọn Filistini, o si damu wọn, o si pa wọn niwaju Israeli. 11 Awọn ọkunrin Israeli si jade kuro ni Mispe, nwọn si le awọn Filistini, nwọn si npa wọn titi nwọn fi de abẹ Betkari. 12 Samueli si mu okuta kan, o si gbe e kalẹ lagbedemeji Mispe ati Seni, o si pe orukọ rẹ̀ ni Ebeneseri, wipe: Titi de ihin li Oluwa ràn wa lọwọ́. 13 Bẹ̃li a tẹ ori awọn Filistini ba, nwọn kò si tun wá si agbegbe Israeli mọ: ọwọ́ Oluwa si wà ni ibi si awọn Filistini, ni gbogbo ọjọ Samueli. 14 Ilu wọnni eyi ti awọn Filistini ti gbà lọwọ Israeli ni nwọn si fi fun Israeli, lati Ekroni wá titi o fi de Gati; ati agbegbe rẹ̀, ni Israeli gbà silẹ lọwọ́ awọn Filistini. Irẹpọ si wà larin Israeli ati awọn Amori. 15 Samueli ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ọjọ rẹ̀. 16 Lati ọdun de ọdun li on ima lọ yika Beteli, ati Gilgali, ati Mispe, on si ṣe idajọ Israeli ni gbogbo ibẹ wọnni. 17 On a si ma yipada si Rama: nibẹ ni ile rẹ̀ gbe wà; nibẹ na li on si ṣe idajọ Israeli, o si tẹ pẹpẹ nibẹ fun Oluwa.

1 Samueli 8

Àwọn Ọmọ Israẹli Bèèrè fún Ọba

1 O si ṣe, nigbati Samueli di arugbo, on si fi awọn ọmọ rẹ̀ jẹ onidajọ fun Israeli. 2 Orukọ akọbi rẹ̀ njẹ Joeli; orukọ ekeji rẹ̀ si njẹ Abia: nwọn si nṣe onidajọ ni Beerṣeba. 3 Awọn ọmọ rẹ̀ kò si rin ni ìwa rẹ̀, nwọn si ntọ̀ erekere lẹhin, nwọn ngbà abẹtẹlẹ, nwọn si nyi idajọ po. 4 Gbogbo awọn agbà Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn si tọ Samueli lọ si Rama, 5 Nwọn si wi fun u pe, Kiye si i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ kò si rin ni ìwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède. 6 Ṣugbọn ohun na buru loju Samueli, nitori ti nwọn wipe, Fi ọba fun wa ki o le ma ṣe idajọ wa, Samueli si gbadura si Oluwa. 7 Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn. 8 Gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti nwọn ṣe lati ọjọ ti mo ti mu nwọn jade ti Egipti wá, titi o si fi di oni, bi nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn si nsin awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni nwọn ṣe si ọ pẹlu. 9 Njẹ nitorina gbọ́ ohùn wọn: ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn. 10 Samueli si sọ gbogbo ọ̀rọ Oluwa fun awọn enia na ti o mbere ọba lọwọ́ rẹ̀. 11 O si wipe, Eyi ni yio ṣe ìwa ọba na ti yio jẹ lori nyin: yio mu awọn ọmọkunrin nyin, yio si yàn wọn fun ara rẹ̀ fun awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati fun ẹlẹṣin rẹ̀, nwọn o si ma sare niwaju kẹkẹ́ rẹ̀. 12 Yio si yan olori ẹgbẹgbẹrun fun ara rẹ̀, ati olori aradọta; yio si yàn wọn lati ma ro oko rẹ̀, ati lati ma kore fun u, ati lati ma ṣe ohun elo-ogun rẹ̀, ati ohun elo-kẹkẹ́ rẹ̀. 13 On o si mu ninu ọmọbinrin nyin ṣe olùṣe ikunra õrun didùn, ati ẹniti yio ma ṣe alasè, ati ẹniti yio ma ṣe akara. 14 Yio mu ninu oko nyin, ati ninu ọgba ajara nyin, ati ninu igi olifi nyin wọnni, ani eyiti o dara julọ ninu wọn, yio si fi fun awọn ẹrú rẹ̀. 15 On o si mu idamẹwa ninu irugbin nyin, ati ọgbà ajara nyin, yio si fi fun awọn ẹmẹ̀wa rẹ̀ ati fun awọn ẹrú rẹ̀. 16 Yio mu awọn ẹrúkunrin nyin, ati ẹrubirin nyin, ati awọn aṣàyàn ọdọmọkunrin nyin, ati awọn kẹtẹkẹtẹ nyin, yio si fi nwọn si iṣẹ ara rẹ̀. 17 On o si mu idamẹwa ninu awọn agutan nyin: ẹnyin o si jasi ẹrú rẹ̀. 18 Ẹnyin o kigbe fun igbala li ọjọ na nitori ọba nyin ti ẹnyin o yàn: Oluwa kì yio gbọ́ ti nyin li ọjọ na. 19 Ṣugbọn awọn enia na kọ̀ lati gbọ́ ohùn Samueli; nwọn si wipe, bẹ̃kọ; awa o ni ọba lori wa; 20 Ani awa o si dabi gbogbo orilẹ-ède; ki ọba wa ki o si ma ṣe idajọ wa, ki o si ma ṣaju wa, ki o si ma ja ogun wa. 21 Samueli si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ awọn enia na, o si sọ wọn li eti Oluwa. 22 Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn wọn ki o si fi ọba jẹ fun wọn. Samueli sọ fun awọn ọmọ Israeli pe. Lọ, olukuluku si ilu rẹ̀.

1 Samueli 9

Saulu pàdé Samuẹli

1 NJẸ ọkunrin kan ara Benjamini si wà, a ma pe orukọ rẹ̀ ni Kiṣi, ọmọ Abeli, ọmọ Sesori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afia, ara Benjamini ọkunrin alagbara. 2 On si ni ọmọkunrin kan, ẹniti a npè ni Saulu, ọdọmọkunrin ti o yàn ti o si ṣe arẹwa, kò si si ẹniti o dara ju u lọ ninu gbogbo awọn ọmọ Israeli: lati ejika rẹ̀ lọ si oke, o ga jù gbogbo awọn enia na lọ. 3 Kẹtẹkẹtẹ Kiṣi baba Saulu si nù. Kiṣi si wi fun Saulu ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ mu ọkan ninu awọn iranṣẹkunrin pẹlu rẹ ki o si dide lọ wá kẹtẹkẹtẹ wọnni. 4 On kọja niha oke Efraimu, o si kọja niha ilẹ Saliṣa, ṣugbọn nwọn kò ri wọn: nwọn si kọja ni ilẹ Salimu, nwọn kò si si nibẹ; o si kọja ni ilẹ Benjamini, nwọn kò si ri wọn. 5 Nigbati nwọn de ilẹ Sufu, Saulu wi fun iranṣẹ-kọnrin rẹ̀ ẹniti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a yipada; ki baba mi ki o má ba fi ãjò awọn kẹtẹkẹtẹ silẹ, ki o si ma kọ ominu nitori wa. 6 O si wi fun u pe, Kiye si i, ẹni Ọlọrun kan wà ni ilu yi, o si ṣe ọkunrin ọlọla; gbogbo eyi ti o ba wi, a si ṣẹ: wá, ki a lọ si ibẹ̀; bọya yio fi ọ̀na ti a o gbà hàn wa. 7 Saulu si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Bi awa ba lọ, kili awa o mu lọ fun ọkunrin na? nitoripe akara tan ni apò wa, ko si si ọrẹ ti a o mu tọ̀ ẹni Ọlọrun na: kili awa ni? 8 Iranṣẹ na si da Saulu lohùn wipe, Mo ni idamẹrin ṣekeli fadaka lọwọ́, eyi li emi o fun ẹni Ọlọrun na, ki o le fi ọ̀na wa hàn wa. 9 (Ni Israeli latijọ, nigbati ọkunrin kan ba lọ bere lọdọ Ọlọrun, bayi ni ima wi, Wá, ẹ jẹ ki a lọ sọdọ arina na, nitori ẹni ti a npe ni woli nisisiyi, on ni a npe ni arina nigba atijọ ri) 10 Nigbana ni Saulu wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Iwọ wi rere; wá, jẹ ki a lọ. Bẹ̃ni nwọn si lọ si ilu na nibiti ẹni Ọlọrun nã gbe wà. 11 Bi nwọn ti nlọ si oke ilu na, nwọn ri awọn wundia ti nlọ fa omi, nwọn bi wọn lere wipe, Arina mbẹ nihin bi? 12 Nwọn si da wọn lohùn, nwọn si wipe, O mbẹ; wo o, o mbẹ niwaju nyin: yara nisisiyi nitoripe loni li o de ilu; nitoriti ẹbọ mbẹ fun awọn enia loni ni ibi giga. 13 Bi ẹnyin ti nlọ si ilu na, ẹnyin o si ri i, ki o to lọ si ibi giga lati jẹun: nitoripe awọn enia kì yio jẹun titi on o fi de, nitori on ni yio sure si ẹbọ na; lẹhin eyini li awọn ti a pè yio to jẹun. Ẹ goke lọ nisisiyi; lakoko yi ẹnyin o ri i. 14 Nwọn goke lọ si ilu na: bi nwọn si ti nwọ ilu na, kiye si i, Samueli mbọ̀ wá pade wọn, lati goke lọ si ibi giga na, 15 Oluwa ti wi leti Samueli ni ijọ kan ki Saulu ki o to de, wipe, 16 Niwoyi ọla emi o ran ọkunrin kan lati ilẹ Benjamini wá si ọ, iwọ o si da ororo si i lori ki o le jẹ olori-ogun Israeli awọn enia mi, yio si gbà awọn enia mi là lọwọ awọn Filistini: nitori emi ti bojuwo awọn enia mi, nitoripe ẹkun wọn ti de ọdọ mi. 17 Nigbati Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun u pe, Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rẹ̀ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi. 18 Saulu si sunmọ Samueli li ẹnu-ọna ilu, o si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ ọ, nibo ni ile arina gbe wà? 19 Samueli da Saulu lohùn o si wipe, emi ni arina na: goke lọ siwaju mi ni ibi giga, ẹ o si ba mi jẹun loni, li owurọ̀ emi o si jẹ ki o lọ, gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ li emi o sọ fun ọ. 20 Niti awọn kẹtẹkẹtẹ rẹ ti o ti nù lati iwọn ijọ mẹta wá, má fi ọkàn si wọn; nitoriti nwọn ti ri wọn. Si tani gbogbo ifẹ, Israeli wà? Ki iṣe si ọ ati si ile baba rẹ? 21 Saulu si dahùn o si wipe, Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israeli? idile mi kò si rẹhìn ninu gbogbo ẹya Benjamini? ẽsi ti ṣe ti iwọ sọrọ yi si mi? 22 Samueli si mu Saulu ati iranṣẹ rẹ̀, o si mu wọn wọ inu gbàngàn, o si fun wọn ni ijoko lãrin awọn agbagba ninu awọn ti a pè, nwọn si to ọgbọ̀n enia. 23 Samueli si wi fun alase pe, Mu ipin ti mo ti fi fun ọ wá, eyi ti mo ti sọ fun ọ pe, Ki o fi i pamọ sọdọ rẹ. 24 Alase na si gbe ejika na, ati eyi ti o wà lori rẹ̀, o si gbe e kalẹ niwaju Saulu. Samueli si wipe, Wo eyi ti a fi silẹ! fà a sọdọ rẹ, ki o si ma jẹ: nitoripe titi di isisiyi li ati pa a mọ fun ọ lati igbati mo ti wipe, emi ti pe awọn enia na. Bẹ̃ni Saulu si ba Samueli jẹun li ọjọ na. 25 Nigbati nwọn sọkalẹ lati ibi giga nì wá si ilu, Samueli si ba Saulu sọrọ lori orule.

Samuẹli ta òróró sí Saulu lórí láti yàn án ní ọba

26 Nwọn si dide ni kutukutu: o si ṣe, li afẹmọjumọ, Samueli si pe Saulu sori orule, wipe, Dide, emi o si ran ọ lọ. Saulu si dide, awọn mejeji sì jade, on ati Samueli, si gbangba. 27 Bi nwọn si ti nsọkalẹ lọ si ipẹkun ilu na, Samueli wi fun Saulu pe, Wi fun iranṣẹ ki o kọja si iwaju wa, (o si kọja) ṣugbọn ki iwọ ki o duro diẹ, ki emi ki o le fi ọ̀rọ Ọlọrun hàn ọ́.

1 Samueli 10

1 SAMUELI si mu igo ororo, o si tu u si i li ori, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si wipe, Kò ṣepe nitoriti Oluwa ti fi ororo yàn ọ li olori ini rẹ̀? 2 Nigbati iwọ ba lọ kuro lọdọ mi loni, iwọ o ri ọkunrin meji li ẹba iboji Rakeli li agbegbe Benjamini, ni Selsa; nwọn o si wi fun ọ pe, Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá: si wõ, baba rẹ ti fi ọran ti kẹtẹkẹtẹ silẹ, o si kọ ominu nitori rẹ wipe, Kili emi o ṣe niti ọmọ mi? 3 Iwọ o si kọja lati ibẹ lọ, iwọ o si de pẹtẹlẹ Tabori, nibẹ li ọkunrin mẹta ti nlọ sọdọ Ọlọrun ni Beteli yio pade rẹ, ọkan yio mu, ọmọ ewurẹ mẹta lọwọ, ekeji yio mu iṣù akara mẹta, ati ẹkẹta yio mu igo ọti-waini. 4 Nwọn o si ki ọ, nwọn o si fi iṣù akara meji fun ọ; iwọ o si gbà a lọwọ wọn. 5 Lẹhin eyini iwọ o wá si oke Ọlọrun, nibiti ẹgbẹ ogun awọn Filistini wà; yio si ṣe, nigbati iwọ ba de ilu na, iwọ o si pade ẹgbẹ woli ti yio ma sọkalẹ lati ibi giga nì wá; nwọn o si ni psalteri, ati tabreti, ati fère, ati harpu niwaju wọn, nwọn o si ma sọtẹlẹ. 6 Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ o si ma ba wọn sọtẹlẹ, iwọ o si di ẹlomiran. 7 Yio si ri bẹ̃, nigbati àmi wọnyi ba de si ọ, ṣe fun ara rẹ ohun gbogbo ti ọwọ́ rẹ ba ri lati ṣe, nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ. 8 Iwọ o si ṣaju mi sọkalẹ lọ si Gilgali, si kiye si i, emi o sọkalẹ tọ ọ wá, lati rubọ sisun, ati lati ru ẹbọ irẹpọ̀: ni ijọ meje ni iwọ o duro, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe han ọ. 9 O si ri bẹ̃ pe, nigbati o yi ẹhin rẹ̀ pada lati lọ kuro lọdọ Samueli, Ọlọrun si fun u li ọkàn miran: gbogbo àmi wọnni si ṣẹ li ọjọ na. 10 Nigbati nwọn si de ibẹ si oke na, si kiye si i, ẹgbẹ awọn woli pade rẹ̀, Ẹmi Ọlọrun si bà le e, on si sọtẹle larin wọn. 11 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ ri pe o nsọtẹlẹ larin awọn woli, awọn enia si nwi fun ara wọn pe, Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu? 12 Ẹnikan lati ibẹ na wá si dahùn, o si wipe, ṣugbọn tani baba wọn? Bẹ̃li o si wà li owe, Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu? 13 Nigbati o sọtẹlẹ tan, o si lọ si ibi giga nì. 14 Arakunrin Saulu kan si wi fun u ati fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Nibo li ẹnyin ti lọ? On si wipe, lati wá awọn kẹtẹkẹtẹ ni: nigbati awa ri pe nwọn kò si nibi kan, awa si tọ Samueli lọ. 15 Arakunrin Saulu na si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ̀ ọ, ohun ti Samueli wi fun ọ. 16 Saulu si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, On ti sọ fun wa dajudaju pe, nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ nã. Ṣugbọn ọ̀ran ijọba ti Samueli sọ, on kò sọ fun u.

Wọ́n fi ìhó Ayọ̀ gba Saulu ní Ọba

17 Samueli si pe gbogbo enia jọ siwaju Oluwa ni Mispe. 18 O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi mu Israeli goke ti Egipti wá, mo si gbà nyin kuro lọwọ́ awọn ara Egipti, ati kuro lọwọ́ gbogbo ijọba wọnni ti o pọn nyin loju. 19 Ẹnyin si kọ̀ Ọlọrun nyin loni, ẹniti on tikara rẹ́ ti gbà nyin kuro lọwọ́ gbogbo awọn ọta nyin, ati gbogbo wahala nyin; ẹnyin si ti wi fun u pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn awa nfẹ ki o fi ẹnikan jọba lori wa. Nisisiyi ẹ duro niwaju Oluwa nipa ẹyà nyin, ati nipa ẹgbẹgbẹrun nyin. 20 Samueli si mu ki gbogbo ẹya Israeli sunmọ tosi, a si mu ẹya Benjamini. 21 On si mu ki ẹya Benjamini sunmọ tosi nipa idile wọn, a mu idile Matri, a si mu Saulu ọmọ Kiṣi: nigbati nwọn si wá a kiri, nwọn kò si ri i. 22 Nitorina nwọn si tun bere lọdọ Oluwa sibẹ bi ọkunrin na yio wá ibẹ̀. Oluwa si dahùn wipe, Wõ, o pa ara rẹ̀ mọ lãrin ohun-elò. 23 Nwọn sare, nwọn si mu u lati ibẹ̀ wá: nigbati o si duro lãrin awọn enia na, o si ga jù gbogbo wọn lọ lati ejika rẹ̀ soke. 24 Samueli si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹnyin kò ri ẹniti Oluwa yàn fun ara rẹ̀, pe, ko si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo enia na? Gbogbo enia si ho ye, nwọn si wipe, Ki Ọba ki o pẹ! 25 Samueli si sọ ìwa ijọba fun awọn enia na. O si kọ ọ sinu iwe, o si fi i siwaju Oluwa. Samueli si rán gbogbo enia na lọ, olukuluku si ile rẹ̀. 26 Saulu pẹlu si lọ si ile rẹ̀ si Gibea; ẹgbẹ awọn alagbara ọkunrin si ba a lọ, ọkàn awọn ẹniti Ọlọrun tọ́. 27 Ṣugbọn awọn ọmọ Beliali wipe, Ọkunrin yi yio ti ṣe gbà wa? Nwọn kẹgàn rẹ̀, nwọn ko si mu ọrẹ wá fun u. On si dakẹ.

1 Samueli 11

Saulu Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni

1 NAHAṢI ara Ammoni si goke wá, o si do ti Jabeṣi-Gileadi: gbogbo ọkunrin Jabeṣi si wi fun Nahaṣi, pe, Ba wa da majẹmu, awa o si ma sìn ọ. 2 Nahaṣi ara Ammoni na si da wọn lohùn pe, Nipa bayi li emi o fi ba nyin da majẹmu, nipa yiyọ gbogbo oju ọtun nyin kuro, emi o si fi i ṣe ẹlẹyà li oju gbogbo Israeli. 3 Awọn agba Jabeṣi si wi fun u pe, Fun wa li ayè ni ijọ meje, awa o si ran onṣẹ si gbogbo agbegbe Israeli bi ko ba si ẹniti yio gbà wa, awa o si jade tọ ọ wá. 4 Awọn iranṣẹ na si wá si Gibea ti Saulu, nwọn rohìn na li eti awọn enia: gbogbo enia na si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun. 5 Si kiye si i, Saulu bọ̀ wá ile lẹhin ọwọ́ malu lati papa wá; Saulu si wipe, Ẽṣe awọn enia ti nwọn fi nsọkun? Nwọn si sọ ọ̀rọ awọn ọkunrin Jabeṣi fun u. 6 Ẹmi Ọlọrun si bà le Saulu nigbati o gbọ́ ọ̀rọ wọnni, inu rẹ̀ si ru pipọ. 7 O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo. 8 O si kà wọn ni Beseki, awọn ọmọ Israeli si jẹ ọkẹ mẹ̃dogun enia; awọn ọkunrin Juda si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun. 9 Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀. 10 Nitorina awọn ọkunrin Jabeṣi wi pe, lọla awa o jade tọ nyin wá, ẹnyin o si fi wa, ṣe bi gbogbo eyi ti o tọ loju nyin. 11 O si ri bẹ̃ lọla na, Saulu si ya awọn enia na si ẹgbẹ mẹta; nwọn si wá ãrin ogun na ni iṣọ owurọ̀, nwọn si pa awọn ara Ammoni titi o fi di igba imoru ọjọ: o si ṣe awọn iyoku fọnka, tobẹ̃ ti meji wọn ko kù ni ibi kan. 12 Awọn enia na si wi fun Samueli, pe, Tani wipe, Saulu yio ha jọba lori wa? mu awọn ọkunrin na wá, a o si pa wọn. 13 Saulu si wi pe, a kì yio pa ẹnikẹni loni yi; nitoripe loni li Oluwa ṣiṣẹ igbala ni Israeli. 14 Nigbana ni Samueli wi fun awọn enia na pe, Wá, ki a lọ si Gilgali, ki a le tun ijọba na ṣe nibẹ. 15 Gbogbo enia na si lọ si Gilgali; nibẹ ni nwọn gbe fi Saulu jọba niwaju Oluwa ni Gilgali: nibẹ ni nwọn gbe ru ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa; nibẹ ni Saulu ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli si yọ ayọ̀ nlanla.

1 Samueli 12

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli

1 SAMUELI wi fun gbogbo Israeli pe, Kiye si i, emi ti gbọ́ ohùn nyin, ninu gbogbo eyi ti ẹnyin wi fun mi, emi si ti fi ẹnikan jọba lori nyin. 2 Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi. 3 Wõ, emi nĩ, jẹri si mi niwaju Oluwa, ati niwaju ẹni ami-ororo rẹ̀: malu tani mo gbà ri? tabi kẹtẹkẹtẹ tani mo gbà ri? tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni ìya ri? tabi lọwọ́ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju? emi o si sãn pada fun nyin. 4 Nwọn si wipe, Iwọ kò rẹ́ wa jẹ ri, bẹ̃ni iwọ kò jẹ ni ni ìya ri, bẹ̃ni iwọ ko gbà nkan lọwọ́ ẹnikẹni wa ri. 5 O si wi fun wọn pe, Oluwa li ẹlẹri si nyin, ati ẹni ami-ororo rẹ̀ ni ẹlẹri loni pe, ẹnyin kò rí nkan lọwọ́ mi. Nwọn si dahùn wipe, On li ẹlẹri. 6 Samueli si wi fun awọn enia na pe, Oluwa li ẹniti o ti yan Mose ati Aaroni, on li ẹni ti o si mu awọn baba nyin goke ti ilẹ Egipti wá. 7 Njẹ nisisiyi ẹ duro jẹ, ki emi ki o le ba nyin sọ̀rọ niwaju Oluwa niti gbogbo iṣẹ ododo Oluwa, eyi ti on ti ṣe fun nyin ati fun awọn baba nyin. 8 Nigbati Jakobu wá si Egipti, ti awọn baba kigbe pe Oluwa, Oluwa si rán Mose ati Aaroni, awọn ẹniti o mu awọn baba nyin ti ilẹ Egypti jade wá, o si mu wọn joko nihinyi. 9 Nwọn si gbagbe Oluwa Ọlọrun wọn, o si tà wọn si ọwọ́ Sisera, olori ogun Hasori, ati si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ ọba Moabu, nwọn si ba wọn jà. 10 Nwọn si kigbe pe Oluwa, nwọn si wipe, Awa ti dẹsẹ̀, nitoripe awa ti kọ̀ Oluwa silẹ, awa si ti nsin Baalimu ati Aṣtaroti: ṣugbọn nisisiyi, gba wa lọwọ́ awọn ọta wa, awa o si sìn ọ. 11 Oluwa si ran Jerubbaali, ati Bedani, ati Jefta ati Samueli, nwọn si gbà nyin lọwọ́ awọn ọta nyin niha gbogbo, ẹnyin si joko li alafia. 12 Nigbati ẹnyin si ri pe Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni tọ̀ nyin wá, ẹnyin wi fun mi pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ọba yio jẹ lori wa: nigbati Oluwa Ọlọrun nyin jẹ ọba nyin. 13 Njẹ nisisiyi wo ọba na ti ẹnyin yàn, ati ti ẹnyin fẹ, kiye si i, Oluwa fi ọba jẹ fun nyin. 14 Bi ẹnyin ba bẹ̀ru Oluwa, ti ẹnyin si sin i, ti ẹnyin si gbọ́ ohùn rẹ̀, ti ẹnyin ko si tapa si ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ati ọba nyin ti o jẹ lori nyin yio ma wà lẹhin Oluwa Ọlọrun nyin. 15 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba gbà ohun Oluwa gbọ́, ti ẹ ba si tàpá si ọ̀rọ Oluwa, ọwọ́ Oluwa yio wà lara nyin si ibi, bi o ti wà lara baba nyin. 16 Nitorina nisisiyi ẹ duro ki ẹ si wo nkan nla yi, ti Oluwa yio ṣe li oju nyin. 17 Oni ki ọjọ ikore ọka bi? emi o kepe Oluwa, yio si ran ãra ati ojò; ẹnyin o si mọ̀, ẹnyin o si ri pe iwabuburu nyin pọ̀, ti ẹnyin ṣe li oju Oluwa ni bibere ọba fun ara nyin. 18 Samueli si kepe Oluwa, Oluwa si ran ãra ati ojò ni ọjọ na: gbogbo enia si bẹru Oluwa pupọ ati Samueli. 19 Gbogbo enia si wi fun Samueli pe, Gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ, ki awa ki o má ba kú: nitori ti awa ti fi buburu yi kun gbogbo ẹṣẹ wa ni bibere ọba fun ara wa. 20 Samueli si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin ti ṣe gbogbo buburu yi: sibẹ ẹ má pada lẹhin Oluwa, ẹ ma fi gbogbo ọkàn nyin sin Oluwa. 21 Ẹ máṣe yipada; nitori yio jasi itẹle ohun asan lẹhin, eyi ti kì yio ni ere; bẹ̃ni kì yio si gbanila; nitori asan ni nwọn. 22 Nitoriti Oluwa kì yio kọ̀ awọn enia rẹ̀ silẹ nitori orukọ rẹ̀ nla: nitoripe o wu Oluwa lati fi nyin ṣe enia rẹ̀. 23 Pẹlupẹlu bi o ṣe ti emi ni, ki a má ri i pe emi si dẹṣẹ̀ si Oluwa ni didẹkun gbadura fun nyin: emi o si kọ́ nyin li ọ̀na rere ati titọ. 24 Ṣugbọn ẹ bẹ̀ru Oluwa, ki ẹ si fi gbogbo ọkàn nyin sin i lododo: njẹ, ẹ ronu ohun nlanla ti o ṣe fun nyin. 25 Ṣugbọn bi ẹnyin ba hu ìwa buburu sibẹ, ẹnyin o ṣegbé t'ẹnyin t'ọba nyin.

1 Samueli 13

Àwọn Ọmọ Israẹli Gbógun ti Àwọn Ará Filistia

1 SAULU jọba li ọdun kan; nigbati o si jọba ọdun meji lori Israeli, 2 Saulu si yan ẹgbẹ̃dogun ọmọkunrin fun ara rẹ̀ ni Israeli; ẹgbã si wà lọdọ Saulu ni Mikmaṣi ati li oke-nla Beteli; ẹgbẹrun si wà lọdọ Jonatani ni Gibea ti Benjamini; o si rán awọn enia ti o kù olukuluku si agọ rẹ̀. 3 Jonatani si pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini ti o wà ninu ile olodi ni Geba, awọn Filistini si gbọ́. Saulu fun ipè yi gbogbo ilẹ na ka, wipe, Jẹ ki awọn Heberu gbọ́. 4 Gbogbo Israeli si gbọ́ pe Saulu pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini, Israeli si di irira fun awọn Filistini. Awọn enia na si pejọ lẹhin Saulu lati lọ si Gilgali. 5 Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni. 6 Awọn ọkunrin Israeli si ri pe, nwọn wà ninu ipọnju (nitoripe awọn enia na wà ninu ìhamọ) nigbana ni awọn enia na fi ara pamọ ninu iho, ati ninu panti, ninu apata, ni ibi giga, ati ninu kanga gbigbẹ. 7 Omiran ninu awọn Heberu goke odo Jordani si ilẹ Gadi ati Gileadi. Bi o ṣe ti Saulu, on wà ni Gilgali sibẹ, gbogbo enia na si nwariri lẹhin rẹ̀. 8 O si duro ni ijọ meje, de akoko ti Samueli dá fun u; ṣugbọn Samueli kò wá si Gilgali, awọn enia si tuka kuro li ọdọ rẹ̀. 9 Saulu si wipe, Mu ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na fun mi wá, o si ru ẹbọ sisun na. 10 O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i. 11 Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi. 12 Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na. 13 Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai. 14 Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ. 15 Samueli si dide, o si lọ lati Gilgali si Gibea ti Benjamini. Saulu si ka awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, o jẹ iwọ̀n ẹgbẹta ọkunrin. 16 Saulu, ati Jonatani ọmọ rẹ̀, ati awọn enia na ti o wà lọdọ wọn si joko ni Gibea ti Benjamini, ṣugbọn awọn Filistini do ni Mikmaṣi. 17 Ẹgbẹ awọn onisùmọ̀mi mẹta jade ni ibudo awọn Filistini: ẹgbẹ kan gbà ọ̀na ti Ofra, si ilẹ Ṣuali. 18 Ẹgbẹ kan si gba ọ̀na Bet-horoni: ati ẹgbẹ kan si gbà ọ̀na agbegbe nì ti o kọju si afonifoji Seboimu ti o wà ni iha iju. 19 Kò si alagbẹdẹ ninu gbogbo ilẹ Israeli: nitori ti awọn Filistini wipe, Ki awọn Heberu ki o má ba rọ idà tabi ọ̀kọ. 20 Ṣugbọn gbogbo Israeli a ma tọ̀ awọn Filistini lọ, olukuluku lati pọ́n doje rẹ̀, ati ọ̀kọ rẹ̀, ati ãke rẹ̀, ati ọ̀ṣọ rẹ̀. 21 Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu. 22 Bẹ̃li o si ṣe li ọjọ ijà, ti a kò ri idà, tabi ọ̀kọ lọwọ ẹnikẹni ninu awọn enia ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani; lọdọ Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ li a ri. 23 Awọn ọmọ-ogun Filistini jade lọ si ikọja Mikmaṣi.

1 Samueli 14

Jonatani hùwà akikanju

1 O si ṣe li ọjọ kan, Jonatani ọmọ Saulu si wi fun ọdọmọkunrin ti o nru ihamọra rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a rekọja lọ si ibudo-ogun awọn Filistini ti o wà niha keji. Ṣugbọn on kò sọ fun baba rẹ̀. 2 Saulu si duro ni iha ipinlẹ Gibea labẹ igi ìbo eyi ti o wà ni Migronu: awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ to iwọn ẹgbẹta ọkunrin. 3 Ahia ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, alufa Oluwa ni Ṣilo, ti nwọ̀ Efodu. Awọn enia na kò si mọ̀ pe Jonatani ti lọ. 4 Larin meji ọ̀na wọnni, eyi ti Jonatani ti nwá lati lọ si ile ọmọ-ogun olodi ti Filistini, okuta mimú kan wà li apa kan, okuta mímú kan si wà li apa keji: orukọ ekini si njẹ Bosesi, orukọ ekeji si njẹ Sene. 5 Ṣonṣo okuta ọkan wà ni ariwa kọju si Mikmaṣi, ti ekeji si wà ni gusù niwaju Gibea. 6 Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là. 7 Ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ na wi fun u pe, Ṣe gbogbo eyi ti o mbẹ li ọkàn rẹ: ṣe bi o ti tọ́ li ọkàn rẹ; wõ, emi wà pẹlu rẹ gẹgẹ bi ti ọkàn rẹ. 8 Jonatani si wi pe, Kiye si i, awa o rekọja sọdọ awọn ọkunrin wọnyi, a o si fi ara wa hàn fun wọn. 9 Bi nwọn ba wi fun wa pe, Ẹ duro titi awa o fi tọ̀ nyin wá; awa o si duro, awa kì yio si goke tọ̀ wọn lọ. 10 Ṣugbọn bi nwọn ba wi pe, Goke tọ̀ wa wá; a o si goke lọ: nitori pe Oluwa ti fi wọn le wa lọwọ́; eyi ni o si jẹ àmi fun wa. 11 Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si. 12 Awọn ọkunrin ile olodi na si da Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, Goke tọ̀ wa wá, awa o si fi nkan hàn nyin; Jonatani si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Ma tọ̀ mi lẹhìn; nitoripe Oluwa ti fi wọn le awọn enia Israeli lọwọ. 13 Jonatani rakò goke, ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lẹhin rẹ̀; awọn Filistini si subu niwaju Jonatani; ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ npa lẹhin rẹ̀. 14 Pipa ikini, eyi ti Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ ṣe, o jasi iwọn ogún ọkunrin ninu abọ iṣẹko kan ti malu meji iba tú. 15 Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla.

Àwọn Ọmọ Ogun Israẹli ṣẹgun Àwọn ti Filistini

16 Awọn ọkunrin ti nṣọ́na fun Saulu ni Gibea ti Benjamini wò; nwọn si ri ọpọlọpọ awọn enia na tuka, nwọn si npa ara wọn bi nwọn ti nlọ. 17 Saulu si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ kà awọn enia na ki ẹ si mọ̀ ẹniti o jade kuro ninu wa. Nwọn si kà, si kiye si i, Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ kò si si. 18 Saulu si wi fun Ahia pe, Gbe apoti Ọlọrun na wá nihinyi. Nitoripe apoti Ọlọrun wà lọdọ awọn ọmọ Israeli li akokò na. 19 O si ṣe, bi Saulu ti mba alufa na sọ̀rọ, ariwo ti o wà ni budo awọn Filistini si npọ̀ si i: Saulu si wi fun alufa na pe, dawọ́ duro. 20 Saulu ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀ ko ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá si oju ija: kiye si i, ida olukuluku si wà li ara ọmọnikeji rẹ̀, rudurudu na si pọ̀ gidigidi. 21 Pẹlupẹlu awọn Heberu ti o wà lọdọ awọn Filistini nigba atijọ, ti o si ti goke ba wọn lọ si budo lati ilu ti o wà yikakiri, awọn na pẹlu si yipada lati dapọ̀ mọ awọn Israeli ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani. 22 Bẹ̃ gẹgẹ nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o ti pa ara wọn mọ ninu okenla Efraimu gbọ́ pe awọn Filistini sa, awọn na pẹlu tẹle wọn lẹhin kikan ni ijà na. 23 Bẹ̃li Oluwa si gbà Israeli là lọjọ na: ija na si rekọja si Bet-afeni.

Àwọn Ohun tí Ó Ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun

24 Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ. 25 Gbogbo awọn ara ilẹ na si de igbo kan, oyin sì wà lori ilẹ na. 26 Nigbati awọn enia si wọ inu igbo na, si kiye si i oyin na nkán; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o mu ọwọ́ rẹ̀ re ẹnu rẹ̀: nitoripe awọn enia bẹ̀ru ifibu na. 27 Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nigbati baba rẹ̀ fi ifibu kilọ fun awọn enia na: o si tẹ ori ọpa ti mbẹ lọwọ rẹ̀ bọ afara oyin na, o si fi i si ẹnu rẹ̀, oju rẹ̀ mejeji si walẹ. 28 Nigbana li ọkan ninu awọn enia na dahùn wipe, baba rẹ ti fi ifibu kilọ fun awọn enia na, pe, ifibu li ọkunrin na ti o jẹ onjẹ li oni. Arẹ̀ si mu awọn enia na. 29 Nigbana ni Jonatani wipe, baba mi yọ ilu li ẹnu, sa wo bi oju mi ti walẹ, nitori ti emi tọ diẹ wò ninu oyin yi. 30 A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to? 31 Nwọn pa ninu awọn Filistini li ọjọ na, lati Mikmaṣi de Aijaloni: o si rẹ̀ awọn enia na gidigidi. 32 Awọn enia sare si ikogun na, nwọn si mu agutan, ati malu, ati ọmọ-malu, nwọn si pa wọn sori ilẹ: awọn enia na si jẹ wọn t'ẹjẹ t'ẹjẹ. 33 Nigbana ni nwọn wi fun Saulu pe, kiye si i, awọn enia na dẹ̀ṣẹ si Oluwa, li eyi ti nwọn jẹ ẹjẹ. On si wipe, Ẹnyin ṣẹ̀ kọja: yi okuta nla fun mi wá loni. 34 Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀. 35 Saulu si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa; eyi ni pẹpẹ ti o kọ ṣe fun Oluwa. 36 Saulu wipe, Ẹ jẹ ki a sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ li oru, ki a ba wọn ja titi di imọlẹ owurọ̀, ẹ má jẹ ki a fi ọkunrin kan silẹ ninu wọn. Nwọn si wipe, Ṣe gbogbo eyi ti o tọ loju rẹ. Nigbana ni alufa ni si wipe, Ẹ jẹ ki a sunmọ ihinyi si Ọlọrun. 37 Saulu si bere lọdọ Ọlọrun pe, ki emi ki o sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ bi? Iwọ o fi wọn lé Israeli lọwọ́ bi? ṣugbọn kò da a lohùn li ọjọ na. 38 Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni. 39 Nitoripe gẹgẹ bi Oluwa ti wà ti o ti gbà Israeli là bi o tilẹ ṣepe a ri i lara Jonatani ọmọ mi, nitõtọ yio kú. Ṣugbọn ninu gbogbo enia na, kò si ẹniti o da a lohùn. 40 Saulu si wi fun gbogbo awọn Israeli pe, Ẹnyin lọ si apakan, emi ati Jonatani ọmọ mi a si lọ si apakan. Gbogbo enia si wi fun Saulu pe, Ṣe eyi ti o tọ ni oju rẹ. 41 Saulu si wi fun Oluwa Ọlọrun Israeli pe, fun mi ni ibò ti o pé. A si mu Saulu ati Jonatani: ṣugbọn awọn enia na yege. 42 Saulu si wipe, Di ibò ti emi ati ti Jonatani ọmọ mi. Ibò na si mu Jonatani. 43 Saulu si wi fun Jonatani pe, Sọ nkan ti o ṣe fun mi. Jonatani si sọ fun u, o si wipe, Nitõtọ mo fi ori ọ̀pá ti mbẹ li ọwọ́ mi tọ́ oyin diẹ wò, wõ emi mura ati kú. 44 Saulu si wipe, ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ pẹlu: nitoripe iwọ Jonatani yio sa kú dandan. 45 Awọn enia si wi fun Saulu pe, Jonatani yio kú, ti o ṣe igbala nla yi ni Israeli? ki a má ri i; bi Oluwa ti wà, ọkan ninu irun ori rẹ̀ kì yio bọ́ silẹ; nitoripe o ba Ọlọrun ṣiṣẹ pọ̀ loni. Bẹ̃li awọn enia si gbà Jonatani silẹ, kò si kú. 46 Saulu si ṣiwọ ati ma lepa awọn Filistini: Awọn Filistini si lọ si ilu wọn.

Ìjọba ati Ìdílé Saulu

47 Saulu si jọba lori Israeli; o si bá gbogbo awọn ọta rẹ̀ jà yika, eyini ni Moabu ati awọn ọmọ Ammoni, ati Edomu, ati awọn ọba Soba ati awọn Filistini: ati ibikibi ti o yi si, a bà wọn ninu jẹ. 48 O si ko ogun jọ, o si kọlu awọn Amaleki, o si gbà Israeli silẹ lọwọ awọn ti o nkó wọn. 49 Awọn ọmọ Saulu si ni Jonatani, ati Iṣui, ati Malkiṣua; ati orukọ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji si ni wọnyi; orukọ akọbi ni Merabu, ati orukọ aburo ni Mikali: 50 Ati orukọ aya Saulu ni Ahinoamu, ọmọbinrin Ahimaasi, ati orukọ olori ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arakunrin baba Saulu. 51 Kiṣi si ni baba Saulu; ati Neri ni baba Abneri ọmọ Abieli. 52 Ogun na si le si awọn Filistini ni gbogbo ọjọ Saulu: bi Saulu ba ri ẹnikan ti o li agbara, tabi akikanju ọkunrin, a mu u sọdọ rẹ̀.

1 Samueli 15

Àwọn Ọmọ Israẹli bá àwọn ará Amaleki Jagun

1 SAMUELI si wi fun Saulu pe, Oluwa rán mi lati fi ami ororo yàn ọ li ọba, lori enia rẹ̀, lori Israeli, nitorina nisisiyi iwọ fetisi ohùn ọ̀rọ Oluwa. 2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ranti eyi ti Amaleki ti ṣe si Israeli, bi o ti lumọ dè e li ọ̀na, nigbati on goke ti Egipti jade wá. 3 Lọ nisisiyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan wọn li aparun, má si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, malu ati agutan, ibakasiẹ ati kẹtẹkẹtẹ. 4 Saulu si ko awọn enia na jọ pọ̀ o si ka iye wọn ni Telaimu, nwọn si jẹ ogun ọkẹ awọn ọkunrin ogun ẹlẹsẹ, pẹlu ẹgbarun awọn ọkunrin Juda. 5 Saulu si wá si ilu-nla kan ti awọn ara Amaleki, o si ba dè wọn li afonifoji kan. 6 Saulu si wi fun awọn Keniti pe, Ẹ lọ, yẹra kuro larin awọn ara Amaleki, ki emi ki o má ba run nyin pẹlu wọn: nitoripe ẹnyin ṣe ore fun gbogbo awọn ọmọ Israeli nigbati nwọn goke ti Egipti wá. Awọn Keniti yẹra kuro larin Amaleki. 7 Saulu si kọlu Amaleki lati Hafila titi iwọ o fi de Ṣuri, ti o wà li apa keji Egipti. 8 O si mu Agagi Ọba Amaleki lãye, o si fi oju ida run gbogbo awọn enia na. 9 Ṣugbọn Saulu ati awọn enia na da Agagi si, ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu malu, ati ohun eyi ti o dara tobẹ̃ ninu wọn, ati ọdọ-agutan abọpa, ati gbogbo nkan ti o dara; nwọn kò si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nkan ti kò dara ti kò si nilari ni nwọn parun patapata.

Ọlọrun kọ Saulu lọ́ba

10 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe, 11 Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na. 12 Nigbati Samueli si dide ni kutukutu owurọ̀ lati pade Saulu, nwọn si sọ fun Samueli pe, Saulu ti wá si Karmeli, sa wõ, on kọ ibi kan fun ara rẹ̀ o si ti lọ, o si kọja siwaju, o si sọkalẹ lọ si Gilgali. 13 Samueli si tọ Saulu wá: Saulu si wi fun u pe, Alabukún ni ọ lati ọdọ Oluwa wá: emi ti ṣe eyi ti Oluwa ran mi. 14 Samueli si wipe, njẹ ewo ni igbe agutan ti emi ngbọ́ li eti mi, ati igbe malu ti emi ngbọ́? 15 Saulu si wi fun u pe, eyi ti nwọn mu ti Amaleki wá ni, ti awọn enia dasi ninu awọn agutan ton ti malu ti o dara julọ lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ; a si pa eyi ti o kù run. 16 Samueli si wi fun Saulu pe, Duro, emi o si sọ eyi ti Oluwa wi fun mi li alẹ yi. On si wi fun u pe, Ma wi. 17 Samueli si wipe, Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli? 18 Oluwa si rán ọ ni iṣẹ, o si wipe, Lọ, ki o si pa awọn ẹlẹṣẹ ara Amaleki run, ki o si ba wọn jà titi o fi run wọn. 19 Eha si ti ṣe ti iwọ kò fi gbọ́ ohùn Oluwa ṣugbọn iwọ si sare si ikogun, ti iwọ si ṣe buburu li oju Oluwa. 20 Saulu si wi fun Samueli pe, Nitotọ, emi gbà ohùn Oluwa gbọ́, emi si ti lọ li ọ̀na ti Oluwa ran mi, emi si ti mu Agagi ọba Amaleki wá, emi si ti pa ara Amaleki run. 21 Ṣugbọn awọn enia na ti mu ninu ikogun, agutan ati malu, pàtaki nkan wọnni ti a ba pa run, lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ ni Gilgali. 22 Samueli si wipe, Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ́? kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilẹ̀ si sàn jù ọra àgbo lọ. 23 Nitoripe iṣọtẹ dabi ẹ̀ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ibọriṣa. Nitoripe iwọ kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, on si kọ̀ ọ li ọba. 24 Saulu si wi fun Samueli pe, Emi ti ṣẹ̀: nitoriti emi ti re ofin Oluwa kọja, ati ọ̀rọ rẹ̀: nitori emi bẹ̀ru awọn enia, emi si gbà ohùn wọn gbọ́. 25 Ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ mi jì mi, ki o sì yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa. 26 Samueli si wi fun Saulu pe, emi kì yio tun yipada pẹlu rẹ mọ nitoriti iwọ ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, Oluwa si ti kọ̀ iwọ lati ma jẹ ọba lori Israeli. 27 Bi Samueli si ti yipada lati lọ, o si di ẹ̀wu ileke rẹ̀ mu, o si faya mọ̃ lọwọ́. 28 Samueli si wi fun u pe, Oluwa fa ijọba Israeli ya kuro lọwọ rẹ loni, o si fi fun aladugbo rẹ kan, ti o sàn ju ọ lọ. 29 Agbara Israeli kì yio ṣeke bẹ̃ni kì yio si ronupiwada: nitoripe ki iṣe ẹda ti yio fi ronupiwada. 30 O si wipe, emi ti dẹ̀ṣẹ: ṣugbọn bu ọlá fun mi, jọwọ, niwaju awọn agbãgbà enia mi, ati niwaju Israeli, ki o si tun yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ. 31 Samueli si yipada, o si tẹle Saulu; Saulu si tẹriba niwaju Oluwa. 32 Samueli si wipe, Mu Agagi ọba awọn ara Amaleki na tọ̀ mi wá nihinyi. Agagi si tọ̀ ọ wá ni idaraya. Agagi si wipe, Nitotọ ikoro ikú ti kọja. 33 Samueli si wipe, Gẹgẹ bi idà rẹ ti sọ awọn obinrin di alaili ọmọ, bẹ̃ gẹgẹ ni iya rẹ yio si di alaili ọmọ larin obinrin. Samueli si pa Agagi niwaju Oluwa ni Gilgali. 34 Samueli si lọ si Rama; Saulu si goke lọ si ile rẹ̀ ni Gibea ti Saulu. 35 Samueli kò si tun pada wá mọ lati wo Saulu titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀: ṣugbọn Samueli kãnu fun Saulu: o si dùn Oluwa nitori on fi Saulu jẹ ọba lori Israeli.

1 Samueli 16

Wọ́n fi àmì Òróró yan Dafidi lọ́ba

1 OLUWA si wi fun Samueli pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kãnu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ̀ ọ lati ma jọba lori Israeli? Fi ororo kún iwo rẹ, ki o si lọ, emi o rán ọ tọ̀ Jesse ara Betlehemu: nitoriti emi ti ri ọba kan fun ara mi ninu awọn ọmọ rẹ̀. 2 Samueli si wi pe, Emi o ti ṣe lọ? bi Saulu ba gbọ́ yio si pa mi. Oluwa si wi fun u pe, mu ọdọ-malu kan li ọwọ́ rẹ, ki o si wipe, Emi wá rubọ si Oluwa. 3 Ki o si pe Jesse si ibi ẹbọ na, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe hàn ọ: iwọ o si ta ororo si ori ẹniti emi o da orukọ fun ọ. 4 Samueli si ṣe eyi ti Oluwa wi fun u, o sì wá si Betlehemu. Awọn agbà ilu na si bẹ̀ru nitori wiwá rẹ̀, nwọn si wipe, Alafia ki iwọ ba wá si bi? 5 On si dahùn wipe, Alafia ni: emi wá rubọ si Oluwa; ẹ ṣe ara nyin ni mimọ́, ki ẹ si wá pẹlu mi si ibi ẹbọ na. On si yà Jesse sí mimọ́, ati awọn ọmọ rẹ̀, o si pe wọn si ẹbọ na. 6 O si ṣe nigbati nwọn de, o ri Eliabu, o si wipe, nitotọ ẹni-àmi-ororo Oluwa mbẹ niwaju rẹ̀. 7 Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn. 8 Jesse si pe Abinadabu, o si mu ki o kọja niwaju Samueli. On si wipe, Oluwa kò si yan eleyi. 9 Jesse si mu ki Ṣamma ki o kọja. On si wipe, Oluwa kò si yàn eyi. 10 Jesse si tun mu ki awọn ọmọ rẹ̀ mejeje kọja niwaju Samueli. Samueli si wi fun Jesse pe, Oluwa kò yan awọn wọnyi. 11 Samueli si bi Jesse lere pe, gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi? On si dahun wipe, abikẹhin wọn li o kù, sa wõ, o nṣọ agutan. Samueli si wi fun Jesse pe, Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa kì yio joko titi on o fi dé ihinyi. 12 O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi. 13 Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.

Dafidi ní Ààfin Saulu

14 Ṣugbọn Ẹmi Oluwa fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa si nyọ ọ li ẹnu. 15 Awọn iranṣẹ Saulu si wi fun u pe, Jọwọ, sa wõ ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun nyọ ọ li ẹnu. 16 Njẹ ki oluwa wa fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà niwaju rẹ̀ lati wá ọkunrin kan ti o mọ̀ ifi duru kọrin: yio si ṣe nigbati ẹmi buburu na lati ọdọ̀ Ọlọrun wá ba de si ọ, yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara dùru, iwọ o si sàn. 17 Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ ba mi wá ọkunrin kan, ti o mọ̀ iṣẹ́ orin daju, ki ẹ si mu u tọ̀ mi wá. 18 Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. 19 Saulu si ran iranṣẹ si Jesse wipe, ran Dafidi ọmọ rẹ si mi, ẹniti o nṣọ agutan. 20 Jesse si mu kẹtẹkẹtẹ, o si di ẹrù akara le e, ati igò ọti-waini, ati ọmọ ewurẹ; o si ran wọn nipa ọwọ Dafidi ọmọ rẹ̀ si Saulu. 21 Dafidi si tọ Saulu lọ, o si duro niwaju rẹ̀: on si fẹ ẹ gidigidi; Dafidi si wa di ẹniti nrù ihamọra rẹ̀. 22 Saulu si ranṣẹ si Jesse pe, Jẹ ki Dafidi, emi bẹ ọ, duro niwaju mi; nitori ti o wù mi. 23 O si ṣe, nigbati ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá ba de si Saulu, Dafidi a si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru: a si san fun Saulu, ara rẹ̀ a si da; ẹmi buburu na, a si fi i silẹ.

1 Samueli 17

Goliati pe Àwọn Ọmọ Israẹli níjà

1 AWỌN Filistini si gbá ogun wọn jọ si oju ijà, nwọn si gba ara wọn jọ si Ṣoko, ti iṣe ti Juda, nwọn si do si Ṣoko ati Aseka, ni Efesdammimi. 2 Saulu ati awọn enia Israeli si gbá ara wọn jọ pọ̀, nwọn si do ni afonifoji Ela, nwọn si tẹ́ ogun de awọn Filistini. 3 Awọn Filistini si duro lori oke kan li apa kan, Israeli si duro lori oke kan li apa keji: afonifoji kan sì wa larin wọn. 4 Akikanju kan si jade lati ibudo awọn Filistini wá, orukọ rẹ̀ ama jẹ Goliati, ara Gati, ẹniti giga rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa ati ibu atẹlẹwọ kan. 5 On si ni akoro idẹ kan li ori rẹ̀, o si wọ̀ ẹ̀wu kan ti a fi idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọn ẹwu na si jẹ ẹgbẹdọgbọn Ṣekeli idẹ. 6 On si ni kobita idẹ li ẹsẹ rẹ̀, ati apata idẹ kan larin ejika rẹ̀. 7 Ọpa ọ̀kọ rẹ̀ si dabi igi awọn awunṣọ, ati ori ọ̀kọ rẹ̀ si jẹ ẹgbẹta oṣuwọn sekeli irin: ẹnikan ti o ru awà kan si nrin niwaju rẹ̀. 8 O si duro o si kigbe si ogun Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin jade lati tẹgun? ṣe Filistini kan li emi iṣe? ẹnyin si jẹ ẹrú Saulu. Ẹnyin yan ọkunrin kan fun ara nyin, ki ẹnyin si jẹ ki o sọkale tọ̀ mi wá. 9 Bi on ba le ba mi ja, ki o si pa mi, nigbana li awa o di ẹrú nyin: ṣugbọn bi emi ba le ṣẹgun rẹ̀, ti emi si pa a, nigbana ni ẹnyin a si di ẹrú wa, ẹnyin o si ma sìn wa. 10 Filistini na si wipe, Emi fi ija lọ̀ ogun Israeli li oni: fi ọkunrin kan fun mi, ki awa mejeji jumọ ba ara wa jà. 11 Nigbati Saulu ati gbogbo Israeli gbọ́ ọ̀rọ Filistini na, nwọn damu, ẹ̀ru nlanla si ba wọn.

Dafidi ní Ibùdó Saulu

12 Dafidi si jẹ ọmọ ara Efrata na ti Betlehemu Juda, orukọ ẹniti ijẹ Jesse; o si ni ọmọ mẹjọ, o si jẹ arugbo larin enia li ọjọ Saulu. 13 Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma. 14 Dafidi si ni abikẹhin: awọn ẹgbọ́n iwaju rẹ̀ mẹtẹta ntọ̀ Saulu lẹhin. 15 Ṣugbọn Dafidi lọ, o si yipada lẹhin Saulu, lati ma tọju agutan baba rẹ̀ ni Betlehemu. 16 Filistini na a si ma sunmọ itosi li owurọ ati li alẹ, on si fi ara rẹ̀ han li ogoji ọjọ. 17 Jesse si wi fun Dafidi ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ, mu agbado didin yi ti ẹfa kan, ati iṣu akara mẹwa yi fun awọn ẹgbọn rẹ, ki o si sure tọ awọn ẹgbọn rẹ ni ibudo; 18 Ki o si mu warakasi mẹwa wọnyi fun oloriogun ẹgbẹrun wọn, ki o si wo bi awọn ẹgbọn rẹ ti nṣe, ki o si gbà nkan àmi wọn wá. 19 Saulu, ati awọn, ati gbogbo ọkunrin Israeli si wà ni afonifoji Ela, nwọn mba awọn Filistini jà. 20 Dafidi si dide ni kutukutu owurọ, o si fi agutan wọnni le olutọju kan lọwọ, o si mura, o si lọ, gẹgẹ bi Jesse ti fi aṣẹ fun u; on si de ibi yàra, ogun na si nlọ si oju ijà, nwọn hó iho ogun. 21 Israeli ati Filistini si tẹgun, ogun si pade ogun. 22 Dafidi si fi nkan ti o nmu lọ le ọkan ninu awọn olutọju nkan gbogbo lọwọ, o si sare si ogun, o tọ awọn ẹgbọn rẹ̀ lọ, o si ki wọn. 23 Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́. 24 Gbogbo ọkunrin Israeli, nigbati nwọn si ri ọkunrin na, nwọn si sa niwaju rẹ̀, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi. 25 Awọn ọkunrin Israeli si wipe, Ẹnyin kò ri ọkunrin yi ti o goke wá ihin? lati pe Israeli ni ijà li o ṣe wá: yio si ṣe pe, ẹniti o ba pa ọkunrin na, ọba yio si fi ọrọ̀ pipọ fun u, yio si fun u li ọmọ rẹ̀ obinrin, yio si sọ ile baba rẹ di omnira ni Israeli. 26 Dafidi si wi fun awọn ọkunrin ti o duro li ọdọ rẹ̀ pe, Kili a o ṣe fun ọkunrin na ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu ẹgàn na kuro li ara Israeli? tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alãye? 27 Awọn enia na si da a li ohùn gẹgẹ bi ọ̀rọ yi pe, Bayi ni nwọn o ṣe fun ọkunrin ti o ba pa a. 28 Eliabu ẹgbọn rẹ̀ si gbọ́ nigbati on ba awọn ọkunrin na sọ̀rọ; Eliabu si binu si Dafidi, o si wipe, Ẽ ti ṣe ti iwọ fi sọkalẹ wá ihinyi, tani iwọ ha fi agutan diẹ nì le lọwọ́ li aginju? emi mọ̀ igberaga rẹ, ati buburu ọkàn rẹ; nitori lati ri ogun ni iwọ ṣe sọkalẹ wá. 29 Dafidi si dahùn wipe, Kini mo ṣe nisisiyi? ko ha ni idi bi? 30 On si yipada kuro lọdọ rẹ̀ si ẹlomiran, o si sọ bakanna: awọn enia na si fi esì fun u gegẹ bi ọ̀rọ iṣaju. 31 Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ti Dafidi sọ, nwọn si sọ gbogbo wọn li oju Saulu: on si ranṣẹ pè e. 32 Dafidi si wi fun Saulu pe, Ki aiya ki o máṣe fò ẹnikẹni nitori rẹ̀; iranṣẹ rẹ yio lọ, yio si ba Filistini yi jà. 33 Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò le tọ Filistini yi lọ lati ba a jà: nitoripe ọdọmọde ni iwọ, on si jẹ jagunjagun lati igba ewe rẹ̀ wá. 34 Dafidi si wi fun Saulu pe, Nigbati iranṣẹ rẹ nṣọ agutan baba rẹ̀, kiniun kan si wá, ati amọtẹkun kan, o si gbe ọdọ agutan kan lati inu agbo. 35 Mo si jade tọ̀ ọ, mo si lù u, mo si gbà a kuro li ẹnu rẹ̀: nigbati o si dide si mi, mo gbá irugbọ̀n rẹ̀ mu, mo si lù u, mo si pa a. 36 Iranṣẹ rẹ pa ati kiniun ati amọtẹkun na: alaikọla Filistini yi yio si dabi ọkan ninu wọn, nitoripe on ti pe ogun Ọlọrun alãye ni ijà. 37 Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ. 38 Saulu si fi gbogbo ihamọra ogun rẹ̀ wọ̀ Dafidi, o si fi ibori idẹ kan bò o li ori; o si fi ẹwu ti a fi irin adarọ pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ. 39 Dafidi si di ida rẹ̀ mọ ihamọra rẹ̀, on si gbiyanju lati lọ, on kò sa iti dan a wò. Dafidi si wi fun Saulu pe, Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rẹ̀. 40 On si mu ọpa rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ̀ ninu odò, o si fi wọn sinu apò oluṣọ agutan ti o ni, ani sinu asùwọn: kànakana rẹ̀ si wà li ọwọ́ rẹ̀; o si sunmọ Filistini na. 41 Filistini na si mbọ̀, o si nsunmọ Dafidi; ati ọkunrin ti o rù awà rẹ̀ si mbọ̀ niwaju rẹ̀. 42 Nigbati Filistini na si wò, ti o si ri Dafidi, o ṣata rẹ̀: nitoripe ọdọmọdekunrin ni iṣe, o pọn, o si ṣe arẹwa enia. 43 Filistini na si wi fun Dafidi pe, Emi ha nṣe aja bi, ti iwọ fi mu ọpá tọ̀ mi wá? Filistini na si fi Dafidi re nipa awọn ọlọrun rẹ̀. 44 Filistini na si wi fun Dafidi pe, Mã bọ̀; emi o si fi ẹran ara rẹ fun awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati fun awọn ẹranko papa. 45 Dafidi si wi fun Filistini na pe, Iwọ mu idà, ati ọ̀kọ, ati awà tọ̀ mi wá; ṣugbọn emi tọ̀ ọ wá li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israeli ti iwọ ti gàn. 46 Loni yi li Oluwa yio fi iwọ le mi lọwọ́, emi o pa ọ, emi o si ke ori rẹ kuro li ara rẹ; emi o si fi okú ogun Filistini fun ẹiyẹ oju ọrun loni yi, ati fun ẹranko igbẹ; gbogbo aiye yio si mọ̀ pe, Ọlọrun wà fun Israeli. 47 Gbogbo ijọ enia yio si mọ̀ daju pe, Oluwa kò fi ida on ọ̀kọ gbà ni la: nitoripe ogun na ti Oluwa ni, yio si fi ọ le wa lọwọ. 48 O si ṣe, nigbati Filistini na dide, ti o nrìn, ti o si nsunmọ tosí lati pade Dafidi, Dafidi si yara, o si sure si ogun lati pade Filistini na. 49 Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ si inu apò, o si mu okuta kan lati ibẹ̀ wá, o si fì i, o si bà Filistini na niwaju, okuta na si wọ inu agbari rẹ̀ lọ, o si ṣubu dojubolẹ. 50 Bẹ̃ni Dafidi si fi kànakàna on okuta ṣẹgun Filistini na, o si bori Filistini na, o si pa a; ṣugbọn idà ko si lọwọ Dafidi. 51 Dafidi si sure, o si duro lori Filistini na, o si mu ida rẹ̀, o si fà a yọ ninu akọ̀ rẹ̀, o si pa a, o si fi idà na bẹ́ ẹ li ori. Nigbati awọn Filistini si ri pe akikanju wọn kú, nwọn si sa. 52 Awọn ọkunrin Israeli ati ti Juda si dide, nwọn si ho yè, nwọn si nle awọn Filistini lọ, titi nwọn fi de afonifoji kan, ati si ojubode Ekronu. Awọn ti o gbọgbẹ ninu awọn Filistini si ṣubu lulẹ li ọ̀na Ṣaaraimu, ati titi de Gati, ati Ekronu. 53 Awọn ọmọ Israeli si pada lati ma lepa awọn Filistini, nwọn si ba budo wọn jẹ. 54 Dafidi si gbe ori Filistini na, o si mu u wá si Jerusalemu; ṣugbọn o fi ihamọra rẹ̀ si inu agọ rẹ̀.

Dafidi níwájú Saulu

55 Nigbati Saulu si ri Dafidi ti nlọ pade Filistini na, o si bi Abneri oloriogun pe, Abneri, ọmọ tani ọmọde yi iṣe? Abneri si dahun pe, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, ọba, emi kò mọ̀. 56 Ọba si wipe, Iwọ bere ọmọ tali ọmọde na iṣe? 57 Bi Dafidi si ti ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, Abneri si mu u wá siwaju Saulu, ti on ti ori Filistini na lọwọ rẹ̀. 58 Saulu si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ ọmọde yi iṣe? Dafidi si da a li ohùn pe, Emi li ọmọ Jesse iranṣẹ rẹ ara Betlehemu.

1 Samueli 18

1 O si ṣe, nigbati o ba Saulu sọ̀rọ tan, ọkàn Jonatani si fà mọ ọkàn Dafidi, Jonatani si fẹ ẹ bi ontikararẹ̀. 2 Saulu si mu u sọdọ lọjọ na, ko si jẹ ki o lọ sọdọ baba rẹ̀ mọ. 3 Jonatani on Dafidi si ba ara wọn mulẹ; nitoripe o fẹ ẹ gẹgẹ bi o ti fẹ ọkàn ara rẹ̀. 4 Jonatani si bọ aṣọ ileke ti o wà li ara rẹ̀ o si fi i fun Dafidi, ati ihamọra rẹ̀, titi de idà rẹ̀, ọrun rẹ̀, ati amure rẹ̀. 5 Dafidi a si ma lọ si ibikibi ti Saulu rán a, a ma huwa ọlọgbọ́n: Saulu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn enia, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Saulu.

Saulu bẹ̀rẹ̀ sí jowú Dafidi

6 O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru. 7 Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀. 8 Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba. 9 Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ. 10 O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu. 11 Saulu si sọ ẹṣín ti o wà lọwọ rẹ̀ na; o si wipe, Emi o pa Dafidi li apa mọ́ ogiri. Dafidi si yẹra kuro niwaju rẹ lẹ̃meji. 12 Saulu si bẹ̀ru Dafidi, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa kọ̀ Saulu. 13 Nitorina Saulu si mu u kuro lọdọ rẹ̀, o si fi i jẹ olori ogun ẹgbẹrun kan, o si nlọ, o si mbọ̀ niwaju awọn enia na. 14 Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. 15 Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀. 16 Gbogbo Israeli ati Juda si fẹ Dafidi, nitoripe a ma lọ a si ma bọ̀ niwaju wọn.

Dafidi fẹ́ Ọmọbinrin Saulu

17 Saulu si wi fun Dafidi pe, Wo Merabu ọmọbinrin mi, eyi agbà, on li emi o fi fun ọ li aya: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alagbara fun mi, ki o si ma ja ija Oluwa. Nitoriti Saulu ti wi bayi pe, Màṣe jẹ ki ọwọ́ mi ki o wà li ara rẹ̀; ṣugbọn jẹ ki ọwọ́ awọn Filistini ki o wà li ara rẹ̀. 18 Dafidi si wi fun Saulu pe, Tali emi, ati ki li ẹmi mi, tabi idile baba mi ni Israeli, ti emi o fi wa di ana ọba. 19 O si ṣe, li akoko ti a ba fi Merabu ọmọbinrin Saulu fun Dafidi, li a si fi i fun Adrieli ara Meholati li aya. 20 Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹran Dafidi, nwọn si wi fun Saulu: nkan na si tọ li oju rẹ̀. 21 Saulu si wipe, Emi o fi i fun u, yio si jẹ idẹkùn fun u, ọwọ́ awọn Filistini yio si wà li ara rẹ̀. Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ o wà di ana mi loni, ninu mejeji. 22 Saulu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ lọ ba Dafidi sọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ pe, Kiyesi i, inu ọba dùn si ọ jọjọ, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ li o si fẹ ọ, njẹ nitorina jẹ ana ọba. 23 Awọn iranṣẹ Saulu si sọ̀rọ wọnni li eti Dafidi. Dafidi si wipe, O ha ṣe nkan ti o fẹrẹ loju nyin lati jẹ ana ọba? Talaka li emi ati ẹni ti a kò kà si. 24 Awọn iranṣẹ Saulu si wa irò fun u, pe, Ọrọ bayi ni Dafidi sọ. 25 Saulu si wipe, Bayi li ẹnyin o sọ fun Dafidi, ọba kò sa fẹ ohun-ana kan bikoṣe ọgọrun ẹfa abẹ Filistini, ati lati gbẹsan lara awọn ọta ọba; ṣugbọn Saulu rò ikú Dafidi lati ọwọ́ awọn Filistini wá. 26 Nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ̀rọ wọnyi fun Dafidi, ohun na si dara li oju Dafidi lati di ana ọba: ọjọ kò si iti pe. 27 Dafidi si dide, o lọ, on ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, o si pa igba ọmọkunrin ninu awọn Filistini; Dafidi si mu ẹfa abẹ wọn wá, nwọn si kà wọn pe fun ọba, ki on ki o le jẹ ana ọba. Saulu si fi Mikali ọmọ rẹ obinrin fun u li aya. 28 Saulu si ri o si mọ̀ pe, Oluwa wà pẹlu Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹ ẹ. 29 Saulu si bẹ̀ru Dafidi siwaju ati siwaju: Saulu si wa di ọtá Dafidi titi. 30 Awọn ọmọ-alade Filistini si jade lọ: o si ṣe, lẹhin igbati nwọn lọ, Dafidi si huwa ọlọgbọ́n ju gbogbo awọn iranṣẹ Saulu lọ; orukọ rẹ̀ si ni iyìn jọjọ.

1 Samueli 19

Saulu fẹ́ pa Dafidi

1 SAULU si sọ fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o pa Dafidi. 2 Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ. 3 Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ. 4 Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ. 5 Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ? 6 Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a. 7 Jonatani si pe Dafidi, Jonatani si ro gbogbo ọràn na fun u. Jonatani si mu Dafidi tọ Saulu wá, on si wà niwaju rẹ̀, bi igbà atijọ. 8 Ogun si tun wà sibẹ, Dafidi si jade lọ, o si ba awọn Filistini jà, o si pa wọn pupọ; nwọn si sa niwaju rẹ̀. 9 Ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa wá si bà le Saulu, o si joko ni ile rẹ̀ ton ti ẹṣín rẹ̀ li lọwọ rẹ̀: Dafidi a si ma fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru. 10 Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na. 11 Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ. 12 Mikali si sọ Dafidi kalẹ lati oju ferese kan wá; on si lọ, o sa, o si fi ara rẹ̀ pamọ. 13 Mikali si mu ere, o si tẹ́ ẹ sori akete, o si fi timtim onirun ewurẹ sibẹ fun irọri rẹ̀, o si fi aṣọ bò o. 14 Nigbati Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi, on si wi fun wọn pe, Kò sàn. 15 Saulu si tun ran awọn onṣẹ na lọ iwo Dafidi, o wi pe, Gbe e goke tọ̀ mi wá ti-akete ti-akete ki emi ki o pa a. 16 Nigbati awọn onṣẹ na de, sa wõ, ere li o si wà lori akete, ati timtim onirun ewurẹ fun irọri rẹ̀. 17 Saulu si wi fun Mikali pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi tàn mi jẹ bẹ̃, ti iwọ si fi jọwọ ọta mi lọwọ lọ, ti on si bọ? Mikali si da Saulu lohùn pe, On wi fun mi pe, Jẹ ki emi lọ; ẽṣe ti emi o fi pa ọ? 18 Dafidi si sa, o si bọ, o si tọ Samueli wá ni Rama, o si rò fun u gbogbo eyi ti Saulu ṣe si i. On ati Samueli si lọ, nwọn si ngbe Naoti. 19 A si wi fun Saulu pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni Naoti ni Rama. 20 Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi: nigbati nwọn ri ẹgbẹ awọn wolĩ ti nsọtẹlẹ, ati Samueli ti o duro bi olori wọn, Ẹmi Ọlọrun si bà le awọn onṣẹ Saulu, awọn na si nsọtẹlẹ. 21 A si ro fun Saulu, o si ran onṣẹ miran, awọn na si nsọtẹlẹ. Saulu si tun ran onṣẹ lẹ̃kẹta, awọn na si nsọtẹlẹ. 22 On na si lọ si Rama, o si de ibi kanga nla kan ti o wà ni Seku: o si bere, o si wipe, Nibo ni Samueli ati Dafidi gbe wà? ẹnikan si wipe, Wõ, nwọn mbẹ ni Naoti ni Rama. 23 On si lọ sibẹ si Naoti ni Rama: Ẹmi Ọlọrun si ba le on na pẹlu, o si nlọ, o si nsọtẹlẹ titi o fi de Naoti ni Rama. 24 On si bọ aṣọ rẹ̀ silẹ, o si sọtẹlẹ pẹlu niwaju Samueli, o si dubulẹ nihoho ni gbogbo ọjọ na, ati ni gbogbo oru na. Nitorina nwọn si wipe, Saulu pẹlu ha wà ninu awọn woli?

1 Samueli 20

Jonatani Ran Dafidi lọ́wọ́

1 DAFIDI si sa kuro ni Naoti ti Rama, o si wá, o si wi li oju Jonatani pe, Kili emi ṣe? kini ìwa buburu mi, ati kili ẹ̀ṣẹ mi li oju baba rẹ, ti o fi nwá ọ̀na ati pa mi. 2 On si wi fun u pe, Ki a má ri i, iwọ kì yio kú: wõ, baba mi ki yio ṣe nkan nla tabi kekere lai sọ ọ li eti mi, njẹ, esi ti ṣe ti baba mi yio fi pa nkan yi mọ fun mi? nkan na kò ri bẹ̃. 3 Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú. 4 Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ, wi, emi o si ṣe e fun ọ. 5 Dafidi si wi fun Jonatani pe, Wõ, li ọla li oṣu titun, emi kò si gbọdọ ṣe alai ba ọba joko lati jẹun; ṣugbọn jẹ ki emi ki o lọ, ki emi si fi ara pamọ li oko titi yio fi di aṣalẹ ijọ kẹta. 6 Bi o ba si ṣepe baba rẹ fẹ mi kù, ki o si wi fun u pe, Dafidi bẹ̀ mi lati sure lọ si Betlehemu ilu rẹ̀: nitoripe ẹbọ ọdun kan kò nibẹ fun gbogbo idile na. 7 Bi o ba wipe, O dara, alafia mbẹ fun iranṣẹ rẹ: ṣugbọn bi o ba binu pupọ, njẹ ki iwọ ki o mọ̀ daju pe buburu ni o nrò ninu rẹ̀. 8 Iwọ o si ṣe ore fun iranṣẹ rẹ, nitoripe iwọ ti mu iranṣẹ rẹ wọ inu majẹmu Oluwa pẹlu rẹ; ṣugbọn bi ìwa buburu ba mbẹ li ọwọ mi, iwọ tikararẹ pa mi; ẽṣe ti iwọ o fi mu mi tọ baba rẹ lọ? 9 Jonatani si wipe, Ki eyini ki o jina si ọ: nitoripe bi emi ba mọ̀ daju pe baba mi npete ibi ti yio wá sori rẹ, njẹ emi le iṣe alaisọ ọ fun ọ bi? 10 Nigbana ni Dafidi wi fun Jonatani pe, Tani yio sọ fun mi? tabi yio ti ri bi baba rẹ ba si fi ìjãnu da ọ lohùn. 11 Jonatani si wi fun Dafidi pe, Wá, jẹ ki a jade lọ si pápá. Awọn mejeji si jade lọ si pápá. 12 Jonatani si wi fun Dafidi pe, Oluwa Ọlọrun Israeli, nigbati mo ba si lu baba mi li ohùn gbọ́ li ọla tabi li ọtunla, si wõ, bi ire ba wà fun Dafidi, ti emi kò ba si ranṣẹ si ọ, ti emi kò si sọ ọ li eti rẹ. 13 Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi. 14 Ki iṣe kiki igbà ti mo wà lãye ni iwọ o si ṣe ãnu Oluwa fun mi, ki emi ki o má kú. 15 Ṣugbọn ki iwọ ki o máṣe mu ãnu rẹ kuro ni ile mi lailai: ki isi ṣe igbati Oluwa ke olukuluku ọtá Dafidi kuro lori ilẹ. 16 Bẹ̃ ni Jonatani bá ile Dafidi da majẹmu wipe, Oluwa yio si bere rẹ̀ lọwọ awọn ọta Dafidi. 17 Jonatani si tun mu ki Dafidi ki o bura nitoriti o sa fẹ ẹ: o si fẹ ẹ bi o ti fẹ ẹmi ara rẹ̀. 18 Nigbana ni Jonatani wi fun Dafidi pe, ọla li oṣu titun: a o si fẹ ọ kù, nitoriti ipò rẹ yio ṣofo. 19 Bi iwọ ba si duro ni ijọ mẹta, nigbana ni iwọ o si yara sọkalẹ, iwọ o si wá si ibiti iwọ gbe ti fi ara rẹ pamọ si nigbati iṣẹ na wà lọwọ, iwọ o si joko ni ibi okuta Eseli. 20 Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan. 21 Si wõ, emi o ran ọmọde-kọnrin kan pe, Lọ, ki o si wá ọfa wọnni. Bi emi ba tẹnu mọ ọ fun ọmọkunrin na, pe, Wõ, ọfa wọnni wà lẹhin rẹ, ṣà wọn wá; nigbana ni iwọ o ma bọ̀; nitoriti alafia mbẹ fun ọ, kò si ewu; bi Oluwa ti wà. 22 Ṣugbọn bi emi ba wi bayi fun ọmọde-kọnrin na pe, Wõ ọfa na mbẹ niwaju rẹ; njẹ ma ba tirẹ lọ; Oluwa li o rán ọ lọ. 23 Niti ọ̀rọ ti emi ati iwọ si ti jumọ sọ, wõ, ki Oluwa ki o wà larin iwọ ati emi titi lailai. 24 Bẹ̃ni Dafidi sì pa ara rẹ̀ mọ li oko; nigbati oṣu titun si de, ọba si joko lati jẹun. 25 Ọba si joko ni ipò rẹ̀ bi igba atijọ lori ijoko ti o gbe ogiri; Jonatani si dide, Abneri si joko ti Saulu, ipò Dafidi si ṣofo. 26 Ṣugbọn Saulu kò sọ nkan nijọ na; nitoriti on rò pe, Nkan ṣe e ni, on ṣe alaimọ́ ni; nitotọ o ṣe alaimọ́ ni. 27 O si ṣe, ni ijọ keji, ti o jẹ ijọ keji oṣu, ipò Dafidi si ṣofo; Saulu si wi fun Jonatani ọmọ rẹ̀ pe, Ẽṣe ti ọmọ Jesse ko fi wá si ibi onjẹ lana ati loni? 28 Jonatani si da Saulu lohùn pe, Dafidi bẹ̀ mi lati lọ si Betlehemu: 29 O si wipe, Jọwọ, jẹ ki emi ki o lọ; nitoripe idile wa li ẹbọ kan iru ni ilu na; ẹgbọn mi si paṣẹ fun mi pe ki emi ki o má ṣaiwà nibẹ; njẹ, bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ rẹ, jọwọ, jẹ ki emi lọ, ki emi ri awọn ẹgbọn mi. Nitorina ni ko ṣe wá si ibi onjẹ ọba. 30 Ibinu Saulu si fà ru si Jonatani, o si wi fun u pe, Iwọ ọmọ ọlọtẹ buburu yi, ṣe emi mọ̀ pe, iwọ ti yàn ọmọ Jesse fun itiju rẹ, ati fun itiju ihoho iya rẹ? 31 Nitoripe ni gbogbo ọjọ ti ọmọ Jesse wà lãye li orilẹ, iwọ ati ijọba rẹ kì yio duro. Njẹ nisisiyi, ranṣẹ ki o si mu u fun mi wá, nitoripe yio kú dandan. 32 Jonatani si da Saulu baba rẹ̀ lohùn, o si wi fun u pe, Nitori kini on o ṣe kú? kili ohun ti o ṣe? 33 Saulu si jù ẹṣín si i lati fi pa a; Jonatani si wa mọ̀ pe baba on ti pinnu rẹ̀ lati pa Dafidi. 34 Bẹ̃ni Jonatani sì fi ibinu dide kuro ni ibi onjẹ, kò si jẹn ní ijọ keji oṣu na: inu rẹ̀ si bajẹ gidigidi fun Dafidi, nitoripe baba rẹ̀ doju tì i. 35 O si ṣe, li owurọ ni Jonatani jade lọ si oko li akoko ti on ati Dafidi ti fi si, ọmọdekunrin kan si wà pẹlu rẹ̀. 36 O si wi fun ọmọdekunrin rẹ̀ pe, sare, ki o si wá ọfà wọnni ti emi o ta. Bi ọmọde na si ti nsare, on si tafa rekọja rẹ̀. 37 Nigbati ọmọdekunrin na si de ibi ọfà ti Jonatani ta, Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na, o si wipe, ọfà na ko ha wà niwaju rẹ bi? 38 Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na pe, Sare, yara, máṣe duro. Ọmọdekunrin Jonatani si ṣa ọfà wọnni, o si tọ̀ oluwa rẹ̀ wá. 39 Ọmọdekunrin na kò si mọ̀ nkan: ṣugbọn Jonatani ati Dafidi li o mọ̀ ọ̀ran na. 40 Jonatani si fi apó ati ọrun rẹ̀ fun ọmọdekunrin rẹ̀, o si wi fun u pe, Lọ, ki o si mu wọn lọ si ilu. 41 Bi ọmọdekunrin na ti lọ tan, Dafidi si dide lati iha gusu, o si wolẹ, o si tẹriba lẹrinmẹta: nwọn si fi ẹnu ko ara wọn li ẹnu, nwọn si jumọ sọkun, ekini keji wọn, titi Dafidi fi bori. 42 Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ma lọ li alafia, bi o ti jẹ pe awa mejeji ti jumọ bura li orukọ Oluwa, pe, Ki Oluwa ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin iru-ọmọ mi ati lãrin iru-ọmọ rẹ lailai. On si dide, o si lọ kuro: Jonatani si lọ si ilu.

1 Samueli 21

Dafidi Sá fún Saulu

1 DAFIDI si wá si Nobu sọdọ Ahimeleki alufa; Ahimeleki si bẹ̀ru lati pade Dafidi, o si wi fun u pe, Eha ti ri ti o fi ṣe iwọ nikan, ati ti kò si fi si ọkunrin kan ti o pẹlu rẹ? 2 Dafidi si wi fun Ahimeleki alufa pe, ọba paṣẹ iṣẹ kan fun mi, o si wi fun mi pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ idi iṣẹ na ti mo rán ọ, ati eyi ti emi ti paṣẹ fun ọ; emi si yàn awọn iranṣẹ mi si ibi bayi. 3 Njẹ kili o wà li ọwọ́ rẹ? fun mi ni ìṣu akara marun li ọwọ́ mi, tabi ohunkohun ti o ba ri. 4 Alufa na si da Dafidi lohùn o si wipe, Kò si akara miran li ọwọ́ mi bikoṣe akara mimọ́; bi awọn ọmọkunrin ba ti pa ara wọn mọ kuro lọdọ obinrin. 5 Dafidi si da alufa na lohùn, o si wi fun u pe, Nitotọ a ti pa ara wa mọ kuro lọdọ obinrin lati iwọn ijọ mẹta wá, ti emi ti jade; gbogbo nkan awọn ọmọkunrin na li o mọ́, ati akara na si wa dabi akara miran, ye e pãpã nigbati o jẹ pe omiran wà ti a yà si mimọ́ loni ninu ohun elo na. 6 Bẹ̃ni alufa na si fi akara mimọ́ fun u; nitoriti kò si akara miran nibẹ bikoṣe akara ifihan ti a ti ko kuro niwaju Oluwa, lati fi akara gbigbona sibẹ li ọjọ ti a ko o kuro. 7 Ọkunrin kan ninu awọn iranṣẹ Saulu si mbẹ nibẹ li ọjọ na, ti a ti da duro niwaju Oluwa; orukọ rẹ̀ si njẹ Doegi, ara Edomu olori ninu awọn darandaran Saulu. 8 Dafidi si tun wi fun Ahimeleki pe, Kò si ọ̀kọ tabi idà lọwọ rẹ nihin? nitoriti emi kò mu idà mi, bẹ̃li emi kò mu nkan ijà mi lọwọ, nitoripe iṣẹ ọba na jẹ́ iṣẹ ikanju. 9 Alufa na si wipe, idà Goliati ara Filistini ti iwọ pa li afonifoji Ela ni mbẹ, wõ, a fi aṣọ kan wé e lẹhin Efodu; bi iwọ o ba mu eyini, mu u; kò si si omiran nihin mọ bikoṣe ọkanna. Dafidi si wipe, Kò si eyiti o dabi rẹ̀, fun mi. 10 Dafidi si dide, o si sa ni ijọ na niwaju Saulu, o si lọ sọdọ Akiṣi, ọba Gati. 11 Awọn iranṣẹ Akiṣi si wi fun u pe, Ṣe eyiyi ni Dafidi ọba ilẹ na? nwọn kò ha ti da ti nwọn si gberin nitori rẹ̀ ni ijo, pe, Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbãrun tirẹ̀? 12 Dafidi si pa ọ̀rọ wọnyi mọ li ọkàn rẹ̀, o si bẹ̀ru Akiṣi ọba Gati gidigidi. 13 On si pa iṣe rẹ̀ dà niwaju wọn, o si sọ ara rẹ̀ di aṣiwere li ọwọ́ wọn, o si nfi ọwọ́ rẹ̀ há ilẹkun oju ọ̀na, o si nwà itọ́ si irungbọn rẹ̀. 14 Nigbana ni Akiṣi wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ẹnyin ri pe ọkunrin na nhuwà aṣiwere; njẹ nitori kini ẹnyin ṣe mu u tọ̀ mi wá? 15 Mo ha ni aṣiwere fi ṣe? ti ẹnyin fi mu eyi tọ̀ mi wá lati hu iwa aṣiwere niwaju mi? eleyi yio ha wọ inu ile mi?

1 Samueli 22

Saulu Pa Àwọn Àlùfáà

1 DAFIDI si kuro nibẹ, o si sa si iho Adullamu; nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ati idile baba rẹ̀ si gbọ́ ọ, nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ nibẹ. 2 Olukuluku ẹniti o ti wà ninu ipọnju, ati olukuluku ẹniti o ti jẹ gbesè, ati olukuluku ẹniti o wà ninu ibanujẹ, si ko ara wọn jọ sọdọ rẹ̀, on si jẹ olori wọn: awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ si to iwọn irinwo ọmọkunrin. 3 Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi. 4 O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na. 5 Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti. 6 Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i; 7 Nigbana ni Saulu wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o duro tì i, pe, Njẹ, ẹ gbọ́, ẹnyin ara Benjamini, ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi? 8 Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi, ti kò fi si ẹnikan ti o sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi ti ba ọmọ Jesse mulẹ, bẹ̃ni kò si si ẹnikan ninu nyin ti o ṣanu mi, ti o si sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi mu ki iranṣẹ mi dide si mi lati ba dè mi, bi o ti ri loni? 9 Doegi ara Edomu ti a fi jẹ olori awọn iranṣẹ Saulu, si dahun wipe, Emi ri ọmọ Jesse, o wá si Nobu, sọdọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. 10 On si bere lọdọ̀ Oluwa fun u, o si fun u li onjẹ o si fun u ni idà Goliati ara Filistia. 11 Ọba si ranṣẹ pe Ahimeleki alufa, ọmọ Ahitubu ati gbogbo idile baba rẹ̀, awọn alufa ti o wà ni Nobu: gbogbo wọn li o si wá sọdọ ọba. 12 Saulu si wipe, Njẹ gbọ́, iwọ ọmọ Ahitubu. On si wipe, Emi nĩ, oluwa mi. 13 Saulu si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dimọlù si mi, iwọ ati ọmọ Jesse, ti iwọ fi fun u li akara, ati idà, ati ti iwọ fi bere fun u lọdọ Ọlọrun, ki on ki o le dide si mi, lati ba dè mi, bi o ti ri loni? 14 Ahimeleki si da ọba lohun, o si wipe, Tali oluwa rẹ̀ ti o ṣe enia re ninu gbogbo awọn iranṣẹ rẹ bi Dafidi, ẹniti iṣe ana ọba, ẹniti o ngbọ́ tirẹ, ti o si li ọla ni ile rẹ? 15 Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ. 16 Ọba si wipe, Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ. 17 Ọba si wi fun awọn aṣaju ti ima sare niwaju ọba, ti o duro tì i, pe, Yipada ki ẹ si pa awọn alufa Oluwa; nitoripe ọwọ́ wọn wà pẹlu Dafidi, ati nitoripe, nwọn mọ̀ igbati on sa, nwọn kò si sọ ọ li eti mi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ ọba ko si jẹ fi ọwọ́ wọn le awọn alufa Oluwa lati pa wọn. 18 Ọba si wi fun Doegi pe, Iwọ, yipada, ki o si pa awọn alufa. Doegi ara Edomu si yipada, o si kọlu awọn alufa, o si pa li ọjọ na, àrunlelọgọrin enia ti nwọ aṣọ ọgbọ̀ Efodu. 19 O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan. 20 Ọkan ninu awọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ti a npè ni Abiatari si bọ́; o si sa asala tọ Dafidi lọ. 21 Abiatari si fi han Dafidi pe, Saulu pa awọn alufa Oluwa tan. 22 Dafidi si wi fun Abiatari pe, emi ti mọ̀ ni ijọ na, nigbati Doegi ara Edomu nì ti wà nibẹ̀ pe, nitotọ yio sọ fun Saulu: nitori mi li a ṣe pa gbogbo idile baba rẹ. 23 Iwọ joko nihin lọdọ mi, máṣe bẹ̀ru, nitoripe ẹniti nwá ẹmi mi, o nwá ẹmi rẹ: ṣugbọn lọdọ mi ni iwọ o wà li ailewu.

1 Samueli 23

Dafidi Gba Ìlú Keila Sílẹ̀

1 NWỌN si wi fun Dafidi pe, Sa wõ awọn ara Filistia mba ara Keila jagun, nwọn si jà ilẹ ipakà wọnni li ole. 2 Dafidi si bere lọdọ Oluwa pe, Ki emi ki o lọ kọlu awọn ara Filistia wọnyi bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe. Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ. 3 Awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ Dafidi si wi fun u pe, Wõ, awa mbẹ̀ru nihinyi ni Juda; njẹ yio ti ri nigbati awa ba de Keila lati fi oju ko ogun awọn ara Filistia? 4 Dafidi si tun bere lọdọ Oluwa. Oluwa si da a lohùn, o si wipe, Dide, ki o sọkalẹ lọ si Keila, nitoripe emi o fi awọn ara Filistia na le ọ lọwọ. 5 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ si Keila, nwọn si ba awọn ara Filistia jà, nwọn si ko ohun ọsìn wọn, nwọn si fi iparun nla pa wọn. Dafidi si gbà awọn ara Keila silẹ. 6 O si ṣe, nigbati Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sa tọ Dafidi lọ ni Keila, o sọkalẹ ton ti efodu kan lọwọ rẹ̀, 7 A si sọ fun Saulu pe, Dafidi wa si Keila. Saulu si wipe, Ọlọrun ti fi i le mi lọwọ; nitoripe a ti dí i mọ tan, nitori o wọ inu ilu ti o ni ilẹkun ati ikere. 8 Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀. 9 Dafidi si mọ̀ pe Saulu ti gbèro buburu si on; o si wi fun Abiatari alufa na pe, Mu efodu na wá nihinyi. 10 Dafidi si wipe Oluwa Ọlọrun Israeli, lõtọ ni iranṣẹ rẹ ti gbọ́ pe Saulu nwá ọ̀na lati wá si Keila, lati wá fọ ilu na nitori mi. 11 Awọn agba ilu Keila yio fi mi le e lọwọ bi? Saulu yio ha sọkalẹ, gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ ti gbọ́ bi? Oluwa Ọlọrun Israeli, emi bẹ̀ ọ, wi fun iranṣẹ rẹ. Oluwa si wipe, Yio sọkalẹ wá. 12 Dafidi si wipe, Awọn agbà ilu Keila yio fi emi ati awọn ọmọkunrin mi le Saulu lọwọ bi? Oluwa si wipe, Nwọn o fi ọ le wọn lọwọ. 13 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ. 14 Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ. 15 Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan. 16 Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun. 17 On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu. 18 Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀. 19 Awọn ara Sifi si goke tọ Saulu wá si Gibea, nwọn si wipe, Ṣe Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o to sa pamọ si ni igbo, ni oke Hakila, ti o wà niha gusu ti Jeṣimoni? 20 Njẹ nisisiyi, Ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ. 21 Saulu si wipe, Alabukun fun li ẹnyin nipa ti Oluwa; nitoripe ẹnyin ti kãnu fun mi. 22 Lọ, emi bẹ̀ nyin, ẹ tun mura, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si ri ibi ti ẹsẹ rẹ̀ gbe wà, ati ẹniti o ri i nibẹ: nitoriti ati sọ fun mi pe, ọgbọ́n li o nlò jọjọ. 23 Ẹ si wò, ki ẹ si mọ̀ ibi isapamọ ti ima sapamọ si, ki ẹ si tun pada tọ mi wá, nitori ki emi ki o le mọ̀ daju; emi o si ba nyin lọ: yio si ṣe, bi o ba wà ni ilẹ Israeli, emi o si wá a li awari ninu gbogbo ẹgbẹrun Juda. 24 Nwọn si dide, nwọn si ṣaju Saulu lọ si Sifi: ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ wà li aginju Maoni, ni pẹtẹlẹ niha gusu ti Jeṣimoni. 25 Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ iwá a. Nwọn si sọ fun Dafidi: o si sọkalẹ wá si ibi okuta kan, o si joko li aginju ti Maoni. Saulu si gbọ́, o si lepa Dafidi li aginju Maoni. 26 Saulu si nrin li apakan oke kan, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ li apa keji oke na: Dafidi si yara lati sa kuro niwaju Saulu; nitoripe Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti rọ̀gba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ka lati mu wọn. 27 Ṣugbọn onṣẹ kan si tọ Saulu wá, o si wipe, iwọ yara ki o si wá, nitoriti awọn Filistini ti gbe ogun tì ilẹ wa. 28 Saulu si pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lọ ipade awọn Filistini: nitorina ni nwọn si se npe ibẹ̀ na ni Selahammalekoti. (ni itumọ rẹ̀, okuta ipinyà.) 29 Dafidi ti goke lati ibẹ lọ, o si joko nibi ti o sapamọ si ni Engedi.

1 Samueli 24

Dafidi dá ẹ̀mí Saulu sí

1 O si ṣe nigbati Saulu pada kuro lẹhin awọn Filistini, a si sọ fun u pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni aginju Engedi. 2 Saulu si mu ẹgbẹdogun akọni ọkunrin ti a yàn ninu gbogbo Israeli, o si lọ lati wá Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ lori okuta awọn ewurẹ igbẹ. 3 O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na. 4 Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu. 5 O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu. 6 On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni. 7 Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ. 8 Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u. 9 Dafidi si wi fun Saulu pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi ngbọ́ ọ̀rọ awọn enia pe, Wõ, Dafidi nwá ẹmi rẹ? 10 Wõ, oju rẹ ri loni, bi Oluwa ti fi iwọ le mi li ọwọ́ loni ni iho nì: awọn kan ni ki emi ki o pa ọ: ṣugbọn emi dá ọ si; emi si wipe, emi ki yio nawọ́ mi si oluwa mi, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa li on iṣe. 11 Pẹlupẹlu, baba mi, wõ, ani wo eti aṣọ rẹ li ọwọ́ mi; nitori emi ke eti aṣọ rẹ, emi ko si pa ọ, si wò, ki o si mọ̀ pe, kò si ibi tabi ẹ̀ṣẹ li ọwọ́ mi, emi kò si ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ ndọdẹ ẹmi mi lati gba a. 12 Ki Oluwa ki o ṣe idajọ larin emi ati iwọ, ati ki Oluwa ki o gbẹsan mi lara rẹ; ṣugbọn ọwọ́ mi ki yio si lara rẹ. 13 Gẹgẹ bi owe igba atijọ ti wi, Ìwabuburu a ma ti ọdọ awọn enia buburu jade wá; ṣugbọn ọwọ́ mi kì yio si lara rẹ. 14 Nitori tani ọba Israeli fi jade? tani iwọ nlepa? okú aja, tabi eṣinṣin? 15 Ki Oluwa ki o ṣe onidajọ, ki o si dajọ larin emi ati iwọ, ki o si wò ki o gbejà mi, ki o si gbà mi kuro li ọwọ́ rẹ. 16 O si ṣe, nigbati Dafidi si dakẹ ọ̀rọ wọnyi isọ fun Saulu, Saulu si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Saulu si gbe ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. 17 O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ. 18 Iwọ si fi ore ti iwọ ti ṣe fun mi hàn loni: nigbati o jẹ pe, Oluwa ti fi emi le ọ li ọwọ́, iwọ kò si pa mi. 19 Nitoripe bi enia ba ri ọta rẹ̀, o le jẹ ki o lọ li alafia bi? Oluwa yio si fi ire san eyi ti iwọ ṣe fun mi loni. 20 Wõ, emi mọ̀ nisisiyi pe, nitotọ iwọ o jẹ ọba, ilẹ-ọba Israeli yio si fi idi mulẹ si ọ lọwọ. 21 Si bura fun mi nisisiyi li orukọ Oluwa, pe, iwọ kì yio ke iru mi kuro lẹhin mi, ati pe, iwọ ki yio pa orukọ mi run kuro ni idile baba mi. 22 Dafidi si bura fun Saulu. Saulu si lọ si ile rẹ̀; ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ si iho na.

1 Samueli 25

Ikú Samuẹli

1 SAMUELI si kú; gbogbo enia Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn sì sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ninu ile rẹ̀ ni Rama. Dafidi si dide, o si sọkalẹ lọ si ijù Parani. 2 Ọkunrin kan si mbẹ ni Maoni, ẹniti iṣẹ rẹ̀ mbẹ ni Karmeli; ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si ni ẹgbẹdogun agutan, ati ẹgbẹrun ewurẹ: o sì nrẹ irun agutan rẹ̀ ni Karmeli. 3 Orukọ ọkunrin na si njẹ Nabali, orukọ aya rẹ̀ si njẹ Abigaili; on si jẹ oloye obinrin, ati arẹwa enia; ṣugbọn onroro ati oniwa buburu ni ọkunrin; ẹni idile Kalebu li on si ṣe. 4 Dafidi si gbọ́ li aginju pe, Nabali nrẹ irun agutan rẹ̀. 5 Dafidi si ran ọmọkunrin mẹwa, Dafidi si sọ fun awọn ọdọmọkunrin na pe, Ẹ goke lọ si Karmeli, ki ẹ si tọ Nabali lọ, ki ẹ si ki i li orukọ mi. 6 Bayi li ẹ o si wi fun ẹniti o wà ni irọra pe, Alafia fun ọ, alafia fun ile rẹ, ati alafia fun ohun gbogbo ti iwọ ni. 7 Njẹ mo gbọ́ pe, awọn olùrẹrun mbẹ lọdọ rẹ; Wõ, awọn oluṣọ agutan rẹ ti wà lọdọ wa, awa kò ṣe wọn ni iwọsi kan, bẹ̃ni ohun kan ko si nù lọwọ wọn, ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni Karmeli. 8 Bi awọn ọmọkunrin rẹ lere, nwọn o si sọ fun ọ. Nitorina jẹ ki awọn ọmọkunrin wọnyi ki o ri oju rere lọdọ rẹ; nitoripe awa sa wá li ọjọ rere: emi bẹ ọ, ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ba bá, fi fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun Dafidi ọmọ rẹ. 9 Awọn ọmọkunrin Dafidi si lọ, nwọn si sọ fun Nabali gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi li orukọ Dafidi, nwọn si simi. 10 Nabali si da awọn iranṣẹ Dafidi lohùn, pe, Tani ijẹ Dafidi? tabi tani si njẹ ọmọ Jesse? ọ̀pọlọpọ iranṣẹ ni mbẹ nisisiyi ti nwọn sá olukuluku kuro lọdọ oluwa rẹ̀. 11 Njẹ ki emi ki o ha mu onjẹ mi, ati omi mi, ati ẹran mi ti mo pa fun awọn olùrẹrun mi, ki emi ki o si fi fun awọn ọkunrin ti emi kò mọ̀ ibi ti nwọn gbe ti wá? 12 Bẹ̃li awọn ọmọkunrin Dafidi si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si pada, nwọn si wá, nwọn si rò fun u gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi. 13 Dafidi si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ki olukuluku nyin ki o di idà rẹ̀ mọ idi. Olukuluku ọkunrin si di idà rẹ̀ mọ idi; ati Dafidi pẹlu si di idà tirẹ̀: iwọn irinwo ọmọkunrin si goke tọ Dafidi lẹhin; igba si joko nibi ẹrù. 14 Ọkan ninu awọn ọmọkunrin Nabali si wi fun Abigaili aya rẹ̀ pe, Wõ, Dafidi ran onṣẹ lati aginju wá lati ki oluwa wa; o si kanra mọ wọn. 15 Ṣugbọn awọn ọkunrin na ṣe ore fun wa gidigidi, nwọn kò ṣe wa ni iwọsi kan, ohunkohun kò nù li ọwọ́ wa, ni gbogbo ọjọ ti awa ba wọn rìn nigbati awa mbẹ li oko. 16 Odi ni nwọn sa jasi fun wa lọsan, ati loru, ni gbogbo ọjọ ti a fi ba wọn gbe, ti a mbojuto awọn agutan. 17 Njẹ si ro o wò, ki o si mọ̀ eyiti iwọ o ṣe; nitoripe ati gbero ibi si oluwa wa, ati si gbogbo ile rẹ̀: on si jasi ọmọ Beliali ti a ko le sọ̀rọ fun. 18 Abigaili si yara, o si mu igba iṣu akara ati igo ọti-waini meji, ati agutan marun, ti a ti sè, ati oṣuwọn agbado yiyan marun, ati ọgọrun idi ajara, ati igba akara eso ọpọtọ, o si di wọn ru kẹtẹkẹtẹ. 19 On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ma lọ niwaju mi; wõ, emi mbọ lẹhin nyin. Ṣugbọn on kò wi fun Nabali bale rẹ̀. 20 O si ṣe, bi o ti gun ori kẹtẹkẹtẹ, ti o si nsọkalẹ si ibi ikọkọ oke na, wõ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nsọ-kalẹ, niwaju rẹ̀; on si wá pade wọn. 21 Dafidi si ti wipe, Njẹ lasan li emi ti pa gbogbo eyi ti iṣe ti eleyi mọ li aginju, ti ohunkohun kò si nù ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀; on li o si fi ibi san ire fun mi yi. 22 Bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ ni ki Ọlọrun ki o ṣe si awọn ọta Dafidi, bi emi ba fi ẹnikẹni ti ntọ̀ sara ogiri silẹ ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀ titi di imọlẹ owurọ. 23 Abigaili si ri Dafidi, on si yara, o sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ, o si dojubolẹ niwaju Dafidi, o si tẹ ara rẹ̀ ba silẹ. 24 O si wolẹ li ẹba ẹsẹ rẹ̀ o wipe, Oluwa mi, fi ẹ̀ṣẹ yi ya mi: ki o si jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ, emi bẹ̀ ọ, sọ̀rọ leti rẹ, ki o si gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ. 25 Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, má ka ọkunrin Beliali yi si, ani Nabali: nitoripe bi orukọ rẹ̀ ti jẹ bẹ̃li on na ri: Nabali li orukọ rẹ̀, aimoye si wà pẹlu rẹ̀; ṣugbọn emi iranṣẹbinrin rẹ kò ri awọn ọmọkunrin oluwa mi, ti iwọ rán. 26 Njẹ, oluwa mi, bi Oluwa ti wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti wà làye, bi Oluwa si ti da ọ duro lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ ara rẹ gbẹsan; njẹ, ki awọn ọta rẹ, ati awọn ẹniti ngbero ibi si oluwa mi ri bi Nabali. 27 Njẹ eyi ni ẹbùn ti iranṣẹbinrin rẹ mu wá fun oluwa mi, jẹ ki a si fi fun awọn ọmọkunrin ti ntọ oluwa mi lẹhin. 28 Emi bẹ̀ ọ, fi irekọja iranṣẹbinrin rẹ ji i: nitori ti Oluwa yio sa ṣe ile ododo fun oluwa mi, nitori ogun Oluwa ni oluwa mi njà; a kò si ri ibi lọwọ rẹ ni gbogbo ọjọ rẹ. 29 Ọkunrin kan si dide lati ma lepa rẹ, ati lati ma wá ẹmi rẹ: ṣugbọn a o si di ẹmi oluwa mi ninu idi ìye lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹmi awọn ọta rẹ li a o si gbọ̀n sọnù gẹgẹ bi kànakana jade. 30 Yio si ṣe, Oluwa yio ṣe si oluwa mi gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti wi nipa tirẹ, yio si yan ọ li alaṣẹ lori Israeli. 31 Eyi ki yio si jasi ibinujẹ fun ọ, tabi ibinujẹ ọkàn fun oluwa mi, nitoripe iwọ ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, tabi pe oluwa mi gbẹsan fun ara rẹ̀: ṣugbọn nigbati Oluwa ba ṣe ore fun oluwa mi, njẹ ranti iranṣẹbinrin rẹ. 32 Dafidi si wi fun Abigaili pe, Alabukun fun Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ran ọ loni yi lati pade mi. 33 Ibukun ni fun ọgbọn rẹ, alabukunfun si ni iwọ, ti o da mi duro loni yi lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ mi gbẹsan fun ara mi. 34 Nitõtọ bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti mbẹ, ti o da mi duro lati pa ọ lara, bikoṣepe bi iwọ ti yara ti o si ti wá pade mi, nitotọ ki ba ti kù fun Nabali di imọlẹ owurọ ninu awọn ti o ntọ̀ sara ogiri. 35 Bẹ̃ni Dafidi si gbà nkan ti o mu wá fun u li ọwọ́ rẹ̀, o si wi fun u pe, Goke lọ li alafia si ile rẹ, wõ, emi ti gbọ́ ohun rẹ, inu mi si dùn si ọ. 36 Abigaili si tọ̀ Nabali wá, si wõ, on si se asè ni ile rẹ̀ gẹgẹ bi ase ọba; inu Nabali si dùn nitoripe, o ti mu ọti li amupara; on kò si sọ nkan fun u, diẹ tabi pupọ: titi di imọlẹ owurọ. 37 O si ṣe; li owurọ, nigbati ọti na si dá tan li oju Nabali, obinrin rẹ̀ si rò nkan wọnni fun u, ọkàn rẹ̀ si kú ninu, on si dabi okuta. 38 O si ṣe lẹhin iwọn ijọ mẹwa, Oluwa lù Nabali, o si kú. 39 Dafidi si gbọ́ pe Nabali kú, o si wi pe, Iyin ni fun Oluwa ti o gbeja gigàn mi lati ọwọ́ Nabali wá, ti o si da iranṣẹ rẹ̀ duro lati ṣe ibi: Oluwa si yi ikà Nabali si ori on tikalarẹ̀. Dafidi si ranṣẹ, o si ba Abigaili sọ̀rọ lati mu u fi ṣe aya fun ara rẹ̀. 40 Awọn iranṣẹ Dafidi si lọ sọdọ Abigaili ni Karmeli, nwọn si sọ fun u pe, Dafidi rán wa wá si ọ lati mu ọ ṣe aya rẹ̀. 41 O si dide, o si dojubolẹ, o si wipe, Wõ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o jẹ iranṣẹ kan lati ma wẹ ẹsẹ awọn iranṣẹ oluwa mi. 42 Abigaili si yara, o dide, o si gun kẹtẹkẹtẹ, awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun si tẹle e lẹhin; on si tẹle awọn iranṣẹ Dafidi, o si wa di aya rẹ̀. 43 Dafidi si mu Ahinoamu ti Jesreeli; awọn mejeji si jẹ aya rẹ̀. 44 Ṣugbọn Saulu ti fi Mikali ọmọ rẹ̀ obinrin, aya Dafidi, fun Falti ọmọ Laisi ti iṣe ara Gallimu.

1 Samueli 26

Dafidi dá ẹ̀mí Saulu sí lẹẹkeji

1 AWỌN ara Sifi si tọ̀ Saulu wá si Gibea, nwọn wipe, Ṣe Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ nibi oke Hakila, eyi ti o wà niwaju Jeṣimoni? 2 Saulu si dide o si sọkalẹ lọ si ijù Sifi, ẹgbẹ̀dogun àṣayàn enia ni Israeli si pẹlu rẹ̀ lati wá Dafidi ni iju Sifi. 3 Saulu si pagọ rẹ̀ ni ibi oke Hakila ti o wà niwaju Jeṣimoni li oju ọ̀na. Dafidi si joko ni ibi iju na, o si ri pe Saulu ntẹle on ni iju na. 4 Dafidi si ran amí jade, o si mọ̀ nitõtọ pe Saulu mbọ̀. 5 Dafidi si dide, o si wá si ibi ti Saulu pagọ si: Dafidi si ri ibi ti Saulu gbe dubulẹ si, ati Abneri ọmọ Neri, olori ogun rẹ̀: Saulu si dubulẹ larin awọn kẹ̀kẹ́, awọn enia na si pagọ wọn yi i ka. 6 Dafidi si dahun, o si wi fun Ahimeleki ọkan ninu awọn ọmọ Heti, ati fun Abiṣai ọmọ Seruia arákùnrin Joabu, pe, Tani o ba mi sọkalẹ lọ sọdọ Saulu ni ibudo? Abiṣai si wipe, emi o ba ọ sọkalẹ lọ. 7 Bẹ̃ni Dafidi ati Abiṣai si tọ awọn enia na wá li oru: si wõ, Saulu dubulẹ o si nsun larin kẹkẹ, a si fi ọ̀kọ rẹ̀ gunlẹ ni ibi timtim rẹ̀: Abneri ati awọn enia na si dubulẹ yi i ka. 8 Abiṣai si wi fun Dafidi pe, Ọlọrun ti fi ọta rẹ le ọ lọwọ loni: njẹ, emi bẹ ọ, sa jẹ ki emi ki o fi ọ̀kọ gun u mọlẹ lẹ̃kan, emi ki yio gun u lẹ̃meji. 9 Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Máṣe pa a: nitoripe tani le nawọ́ rẹ̀ si ẹni-ami-ororo Oluwa ki o si wà laijẹbi? 10 Dafidi si wipe, bi Oluwa ti mbẹ Oluwa yio pa a, tabi ọjọ rẹ̀ yio si pe ti yio kú, tabi on o sọkalẹ lọ si ibi ijà, a si ṣegbe nibẹ. 11 Oluwa má jẹ ki emi nà ọwọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa: njẹ, emi bẹ ọ, mu ọ̀kọ na ti mbẹ nibi timtim rẹ̀, ati igo omi ki a si ma lọ. 12 Dafidi si mu ọ̀kọ na, ati igo omi na kuro nibi timtim Saulu: nwọn si ba ti wọn lọ, kò si si ẹnikan ti o ri i, tabi ti o mọ̀; kò si si ẹnikan ti o ji; gbogbo wọn si sùn; nitoripe orun àjika lati ọdọ Oluwa wá ti ṣubu lù wọn. 13 Dafidi si rekọja si iha keji, o si duro lori oke kan ti o jina rere; afo nla kan si wà lagbedemeji wọn: 14 Dafidi si kọ si awọn enia na, ati si Abneri ọmọ Neri wipe, Iwọ kò dahun, Abneri? Nigbana ni Abneri si dahun wipe, Iwọ tani npe ọba? 15 Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ. 16 Nkan ti iwọ ṣe yi kò dara. Bi Oluwa ti mbẹ, o tọ ki ẹnyin ki o kú, nitoripe ẹnyin ko pa oluwa nyin mọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa. Njẹ si wo ibiti ọ̀kọ ọba gbe wà, ati igò omi ti o ti wà nibi timtim rẹ̀. 17 Saulu si mọ̀ ohùn Dafidi, o si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Dafidi si wipe, Ohùn mi ni, oluwa mi, ọba. 18 On si wipe, Nitori kini oluwa mi ṣe nlepa iranṣẹ rẹ? kili emi ṣe? tabi ìwa buburu wo li o wà li ọwọ́ mi. 19 Njẹ emi bẹ ọ ọba, oluwa mi, gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹ rẹ. Bi Oluwa ba ti ru iwọ soke si mi, jẹ ki on ki o gbà ẹbọ; ṣugbọn bi o ba si ṣepe ọmọ enia ni, ifibu ni ki nwọn ki o jasi niwaju Oluwa; nitori nwọn le mi jade loni ki emi má gbe inu ilẹ ini Oluwa, wipe, Lọ, sin awọn ọlọrun miran. 20 Njẹ máṣe jẹ ki ẹjẹ mi ki o ṣàn silẹ niwaju Oluwa: nitori ọba Israeli jade lati wá itapin bi ẹni ndọdẹ aparo lori oke-nla. 21 Saulu si wipe, Emi ti dẹṣẹ: yipada, Dafidi ọmọ mi: nitoripe emi kì yio wá ibi rẹ mọ, nitoriti ẹmi mi sa ti ṣe iyebiye li oju rẹ loni: wõ, emi ti nhuwa wère mo si ti ṣina jọjọ. 22 Dafidi si dahun, o si wipe, Wo ọ̀kọ̀ ọba! ki o si jẹ ki ọkan ninu awọn ọmọkunrin rekọja wá gbà a. 23 Ki Oluwa ki o san a fun olukuluku ododo rẹ̀ ati otitọ rẹ̀: nitoripe Oluwa ti fi ọ le mi lọwọ loni, ṣugbọn emi ko fẹ nawọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa. 24 Si wõ, gẹgẹ bi ẹmi rẹ ti tobi loni loju mi, bẹni ki ẹmi mi ki o tobi loju Oluwa, ki o si gbà mi lọwọ ibi gbogbo. 25 Saulu si wi fun Dafidi pe, Alabukunfun ni iwọ, Dafidi ọmọ mi: nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori. Dafidi si ba ọ̀na rẹ̀ lọ, Saulu si yipada si ibugbe rẹ̀.

1 Samueli 27

Dafidi láàrin àwọn Ará Filistia

1 DAFIDI si wi li ọkàn ara rẹ̀ pe, njẹ ni ijọ kan l'emi o ti ọwọ́ Saulu ṣegbe, ko si si ohun ti o yẹ mi jù ki emi ki o yara sa asala lọ si ilẹ awọn Filistini: yio su Saulu lati ma tun wá mi kiri ni gbogbo agbegbe Israeli: emi a si bọ li ọwọ́ rẹ̀. 2 Dafidi si dide, o si rekọja, on ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati. 3 Dafidi si ba Akiṣi joko ni Gati, on, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, olukuluku wọn ti on ti ara ile rẹ̀; Dafidi pẹlu awọn aya rẹ̀ mejeji, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili ara Karmeli aya Nabali. 4 A si sọ fun Saulu pe, Dafidi sa lọ si Gati: on ko si tun wá a kiri mọ. 5 Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Bi o ba jẹ pe emi ri ore ọfẹ loju rẹ, jẹ ki wọn ki o fun mi ni ibi kan ninu awọn ileto wọnni; emi o ma gbe ibẹ: ẽṣe ti iranṣẹ rẹ yio si ma ba ọ gbe ni ilu ọba? 6 Akiṣi si fi Siklagi fun u ni ijọ na; nitorina ni Siklagi fi di ti awọn ọba Juda titi o fi di oni yi. 7 Iye ọjọ ti Dafidi fi joko ni ilu awọn Filistini si jẹ ọdun kan ati oṣu mẹrin. 8 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti. 9 Dafidi si kọlu ilẹ na, ko si fi ọkunrin tabi obinrin silẹ lãye, o si ko agùtan, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ, ati aṣọ, o si yipada o si tọ Akisi wá. 10 Akiṣi si bi i pe, Nibo li ẹnyin gbe rìn si loni? Dafidi si dahun pe, Siha gusu ti Juda ni, ati siha gusun ti Jerameeli, ati siha gusu ti awọn ara Keni: 11 Dafidi kò si da ọkunrin tabi obinrin si lãye, lati mu ihin wá si Gati, wipe, Ki nwọn ki o má ba sọ ọ̀rọ wa nibẹ, pe, Bayi ni Dafidi ṣe, ati bẹ̃ni iṣe rẹ̀ yio si ri ni gbogbo ọjọ ti yio fi joko ni ilu awọn Filistini. 12 Akiṣi si gba ti Dafidi gbọ́, wipe, On ti mu ki Israeli ati awọn enia rẹ̀ korira rẹ̀ patapata, yio si jẹ iranṣẹ mi titi lai.

1 Samueli 28

1 O si ṣe, ni ijọ wọnni, awọn Filistini si ko awọn ogun wọn jọ, lati ba Israeli jà. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Mọ̀ dajudaju pe, iwọ o ba mi jade lọ si ibi ija, iwọ ati awọn ọmọkunrin rẹ. 2 Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Nitotọ iwọ o si mọ̀ ohun ti iranṣẹ rẹ le ṣe. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Nitorina li emi o ṣe fi iwọ ṣe oluṣọ ori mi ni gbogbo ọjọ.

Saulu lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Abokùúsọ̀rọ̀

3 Samueli sì ti kú, gbogbo Israeli si sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ni Rama ni ilu rẹ̀. Saulu si ti mu awọn abokusọ̀rọ-ọkunrin, ati awọn abokusọ̀rọ-obinrin kuro ni ilẹ na. 4 Awọn Filistini si ko ara wọn jọ, nwọn wá, nwọn si do si Ṣunemu: Saulu si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si tẹdo ni Gilboa. 5 Nigbati Saulu si ri ogun awọn Filistini na, on si bẹ̀ru, aiya rẹ̀ si warìri gidigidi. 6 Nigbati Saulu si bere lọdọ Oluwa, Oluwa kò da a lohùn nipa alá, nipa Urimu tabi nipa awọn woli. 7 Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ. 8 Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi. 9 Obinrin na si da a lohùn pe, Wõ, iwọ sa mọ̀ ohun ti Saulu ṣe, bi on ti ke awọn abokusọ̀rọ obinrin, ati awọn abokusọ̀rọ ọkunrin kuro ni ilẹ na; njẹ eha ṣe ti iwọ dẹkùn fun ẹmi mi, lati mu ki nwọn pa mi? 10 Saulu si bura fun u nipa Oluwa, pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ìya kan ki yio jẹ ọ nitori nkan yi. 11 Obinrin na si bi i pe, Tali emi o mu wá soke fun ọ? on si wipe, Mu Samueli goke fun mi wá. 12 Nigbati obinrin na si ri Samueli, o kigbe lohùn rara: obinrin na si ba Saulu sọrọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi tan mi jẹ? nitoripe Saulu ni iwọ iṣe. 13 Ọba si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru; kini iwọ ri? obinrin na si wi fun Saulu pe, Emi ri ọlọrun kan nṣẹ́ ti ilẹ wá. 14 O si bi i pe, Ẽ ti ri? o si wipe, Ọkunrin arugbo kan li o nṣẹ́ bọ̀; o si fi agbada bora. Saulu si mọ̀ pe, Samueli ni; o si tẹriba, o si wolẹ. 15 Samueli si wi fun Saulu pe, Eṣe ti iwọ fi yọ mi lẹnu lati mu mi wá oke? Saulu si dahun o si wipe, Ipọnju nla ba mi; nitoriti awọn Filistini mba mi jagun, Ọlọrun si kọ̀ mi silẹ, kò si da mi lohùn mọ, nipa ọwọ́ awọn woli, tabi nipa alá; nitorina li emi si ṣe pè ọ, ki iwọ ki ole fi ohun ti emi o ṣe hàn mi. 16 Samueli si wipe, O ti ṣe bi mi lere nigbati o jẹ pe, Oluwa ti kọ̀ ọ silẹ, o si wa di ọta rẹ? 17 Oluwa si ṣe fun ara rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Oluwa si yà ijọba na kuro li ọwọ́ rẹ, o si fi fun aladugbo rẹ, ani Dafidi. 18 Nitoripe iwọ kò gbọ́ ohùn Oluwa, iwọ kò si ṣe iṣẹ ibinu rẹ̀ si Amaleki, nitorina li Oluwa si ṣe nkan yi si ọ loni yi: 19 Oluwa yio si fi Israeli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi: Oluwa yio si fi ogun Israeli le awọn Filistini lọwọ́. 20 Lojukanna ni Saulu ṣubu lulẹ gbọrọ bi o ti gùn, ẹ̀ru si bà a gidigidi, nitori ọ̀rọ Samueli; agbara kò si si fun u: nitoripe kò jẹun li ọjọ na t'ọsan t'oru. 21 Obinrin na si tọ Saulu wá, o si ri i pe o wà ninu ibanujẹ pupọ, o si wi fun u pe, Wõ, iranṣẹbinrin rẹ ti gbọ́ ohùn rẹ, emi si ti fi ẹmi mi si ọwọ́ mi, emi si ti gbọ́ ọ̀rọ ti iwọ sọ fun mi. 22 Njẹ, nisisiyi, emi bẹ ọ, gbọ́ ohùn iranṣẹbinrin rẹ, emi o si fi onjẹ diẹ siwaju rẹ; si jẹun, iwọ o si li agbara, nigbati iwọ ba nlọ li ọ̀na. 23 Ṣugbọn on kọ̀, o si wipe, Emi kì yio jẹun. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ̀, pẹlu obinrin na si rọ̀ ọ; on si gbọ́ ohùn wọn. O si dide kuro ni ilẹ, o si joko lori akete. 24 Obinrin na si ni ẹgbọrọ malu kan ti o sanra ni ile; o si yara, o pa a o si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara aiwu. 25 On si mu u wá siwaju Saulu, ati siwaju awọn iranṣẹ rẹ̀; nwọn si jẹun. Nwọn si dide, nwọn lọ li oru na.

1 Samueli 29

Àwọn ará Filistia Kọ Dafidi

1 AWỌN Filistini si ko gbogbo ogun wọn jọ si Afeki: Israeli si do ni ibi isun omi ti o wà ni Jesreeli. 2 Awọn ijoye Filistini si kọja li ọrọrun ati li ẹgbẹgbẹrun; Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pẹlu Akiṣi si kẹhin. 3 Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi. 4 Awọn ijoye Filistini si binu si i; awọn ijoye Filistini si wi fun u pe, jẹ ki ọkunrin yi pada ki o si lọ si ipò rẹ̀ ti o fi fun u, ki o má si jẹ ki o ba wa sọkalẹ lọ si ogun, ki o má ba jasi ọta fun wa li ogun; Kini on o fi ba oluwa rẹ̀ laja, ori awọn enia wọnyi kọ? 5 Ṣe eyi ni Dafidi ti nwọn tori rẹ̀ gberin ara wọn ninu ijo wipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbãrun tirẹ̀? 6 Akiṣi si pe Dafidi, o si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, iwọ jẹ olõtọ ati ẹni ìwa rere loju mi, ni alọ rẹ ati abọ̀ rẹ pẹlu mi li ogun; nitoripe emi ko iti ri buburu kan lọwọ rẹ lati ọjọ ti iwọ ti tọ̀ mi wá, titi o fi di oni yi: ṣugbọn loju awọn ijoye iwọ kò ṣe ẹni ti o tọ́. 7 Njẹ yipada ki o si ma lọ li alafia, ki iwọ ki o má ba ṣe ibanujẹ fun awọn Filistini. 8 Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Kili emi ṣe? kini iwọ si ri lọwọ iranṣẹ rẹ lati ọjọ ti emi ti gbe niwaju rẹ titi di oni yi, ti emi kì yio fi lọ ba awọn ọta ọba ja? 9 Akiṣi si dahun o si wi fun Dafidi pe, Emi mọ̀ pe iwọ ṣe ẹni-rere loju mi, bi angeli Ọlọrun: ṣugbọn awọn ijoye Filistini wi pe, On kì yio ba wa lọ si ogun. 10 Njẹ, nisisiyi dide li owurọ pẹlu awọn iranṣẹ oluwa rẹ ti o ba ọ wá: ki ẹ si dide li owurọ nigbati ilẹ ba mọ́, ki ẹ si ma lọ. 11 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si dide li owurọ lati pada lọ si ilẹ awọn Filistini. Awọn Filistini si goke lọ si Jesreeli.

1 Samueli 30

Dafidi bá àwọn ará Amaleki jagun

1 O si ṣe, nigbati Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si bọ̀ si Siklagi ni ijọ kẹta, awọn ara Amaleki si ti kọlu iha ariwa, ati Siklagi, nwọn si ti kun u; 2 Nwọn si ko awọn obinrin ti mbẹ ninu rẹ̀ ni igbekun, nwọn kò si pa ẹnikan, ọmọde tabi agbà, ṣugbọn nwọn ko nwọn lọ, nwọn si ba ọ̀na ti nwọn lọ. 3 Dafidi ati awọn ọmọkunrin si wọ ilu, si wõ, a ti kun u; ati obinrin wọn, ati ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn li a kó ni igbèkun lọ. 4 Dafidi ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun titi agbara kò si si fun wọn mọ lati sọkun. 5 A si kó awọn aya Dafidi mejeji nigbèkun lọ, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili aya, Nabali ara Karmeli. 6 Dafidi si banujẹ gidigidi, nitoripe awọn enia na si nsọ̀rọ lati sọ ọ li okuta, nitoriti inu gbogbo awọn enia na si bajẹ, olukuluku ọkunrin nitori ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati nitori ọmọ rẹ̀ obinrin: ṣugbọn Dafidi mu ara rẹ̀ li ọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rẹ̀. 7 Dafidi si wi fun Abiatari alufa, ọmọ Ahimeleki pe, Emi bẹ̀ ọ, mu efodu fun mi wá nihinyi. Abiatari si mu efodu na wá fun Dafidi. 8 Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà. 9 Bẹni Dafidi ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si lọ, nwọn si wá si ibi odo Besori, apakan si duro. 10 Ṣugbọn Dafidi ati irinwo ọmọkunrin lepa wọn: igba enia ti ãrẹ̀ mu, ti nwọn kò le kọja odò Besori si duro lẹhin. 11 Nwọn si ri ara Egipti kan li oko, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá, nwọn si fun u li onjẹ, o si jẹ; nwọn si fun u li omi mu; 12 Nwọn si bùn u li akara eso ọpọtọ ati ṣiri ajara gbigbẹ meji: nigbati o si jẹ ẹ tan, ẹmi rẹ̀ si sọji: nitoripe ko jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò si mu omi ni ijọ mẹta li ọsan, ati li oru. 13 Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan. 14 Awa si gbe ogun lọ siha gusu ti ara Keriti, ati si apa ti iṣe ti Juda, ati si iha gusu ti Kelebu; awa si kun Siklagi. 15 Dafidi si bi i lere pe, Iwọ le mu mi sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun yi lọ bi? On si wipe, Fi Ọlọrun bura fun mi, pe, iwọ kì yio pa mi, bẹ̃ni iwọ kì yio si fi mi le oluwa mi lọwọ; emi o si mu ọ sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun na lọ. 16 O si mu u sọkalẹ, si wõ, nwọn si tànka ilẹ, nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn si njo, nitori ikogun pupọ ti nwọn ko lati ilẹ awọn Filistini wá, ati lati ilẹ Juda. 17 Dafidi si pa wọn lati afẹmọjumọ titi o fi di aṣalẹ ijọ keji: kò si si ẹnikan ti o là ninu wọn, bikoṣe irinwo ọmọkunrin ti nwọn gun ibakasiẹ ti nwọn si sa. 18 Dafidi si gba gbogbo nkan ti awọn ara Amaleki ti ko: Dafidi si gbà awọn obinrin rẹ̀ mejeji. 19 Kò si si nkan ti o kù fun wọn, kekere tabi nla, ọmọkunrin tabi ọmọbinrin, tabi ikogun, tabi gbogbo nkan ti nwọn ti ko: Dafidi si gbà gbogbo wọn. 20 Dafidi si ko gbogbo agutan, ati malu, nwọn si dà wọn ṣaju nkan miran ti nwọn gbà, nwọn si wipe, Eyiyi ni ikogun ti Dafidi. 21 Dafidi si ba igba ọkunrin ti o ti rẹ̀ jù ati tọ̀ Dafidi lẹhin, ti on ti fi silẹ li odò Besori: nwọn si lọ ipade Dafidi, ati lati pade awọn enia ti o pẹlu rẹ̀: Dafidi si pade awọn enia na, o si ki wọn. 22 Gbogbo awọn enia buburu ati awọn ọmọ Beliali ninu awọn ti o ba Dafidi lọ si dahun, nwọn si wipe, Bi nwọn kò ti ba wa lọ, a kì yio fi nkan kan fun wọn ninu ikogun ti awa rí gbà bikoṣe obinrin olukuluku wọn, ati ọmọ wọn; ki nwọn ki o si mu wọn, ki nwọn si ma lọ. 23 Dafidi si wipe, Ẹ má ṣe bẹ̃, enyin ará mi: Oluwa li o fi nkan yi fun wa, on li o si pa wa mọ, on li o si fi ẹgbẹ-ogun ti o dide si wa le wa lọwọ. 24 Tani yio gbọ́ ti nyin ninu ọ̀ran yi? ṣugbọn bi ipin ẹniti o sọkalẹ lọ si ìja ti ri, bẹ̃ni ipin ẹniti o duro ti ẹrù; nwọn o si pin i bakanna. 25 Lati ọjọ na lọ, o si pa a li aṣẹ, o si sọ ọ li ofin fun Israeli titi di oni yi. 26 Dafidi si bọ̀ si Siklagi, o si rán ninu ikogun na si awọn agbà Juda, ati si awọn ọrẹ́ rẹ̀, o si wipe, Wõ, eyi li ẹ̀bun fun nyin, lati inu ikogun awọn ọta Oluwa wá. 27 O si rán a si awọn ti o wà ni Beteli ati si awọn ti o wà ni gusu Ramoti, ati si awọn ti o wà ni Jattiri. 28 Ati si awọn ti o wà ni Aroeri, ati si awọn ti o wà ni Sifmoti, ati si awọn ti o wà ni Eṣtemoa. 29 Ati si awọn ti o wà ni Rakali, ati si awọn ti o wà ni ilu awọn Jerameeli, ati si awọn ti o wà ni ilu awọn ara Keni, 30 Ati si awọn ti o wà ni Homa, ati si awọn ti o wà ni Koraṣani, ati si awọn ti o wà ni Ataki. 31 Ati si awọn ti o wà ni Hebroni, ati si gbogbo ilu wọnni ti Dafidi tikararẹ̀ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ima rin kiri.

1 Samueli 31

Ikú Saulu ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 AWỌN Filistini si ba Israeli jà: awọn ọkunrin Israeli si sa niwaju awọn Filistini, awọn ti o fi ara pa sì ṣubu li oke Gilboa. 2 Awọn Filistini si nlepa Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kikan; awọn Filistini si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu. 3 Ijà na si buru fun Saulu gidigidi, awọn tafàtafa si ta a li ọfà, o si fi ara pa pupọ li ọwọ́ awọn tafàtafa. 4 Saulu si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Fa ìda rẹ yọ, ki o si fi i gún mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má bà wá gún mi, ati ki wọn ki o má ba fi mi ṣe ẹlẹya. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ ko fẹ ṣe bẹ̃, nitoripe ẹrù ba a gidigidi. Saulu si mu idà na o si fi pa ara rẹ̀. 5 Nigbati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na si fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, o si kú pẹlu rẹ̀. 6 Saulu si kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ẹni ti o rù ihamọra rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀ li ọjọ kanna. 7 Nigbati awọn ọkunrin Israeli ti o wà li apa keji afonifoji na, ati awọn ẹniti o wà li apa keji Jordani, ri pe awọn ọkunrin Israeli sa, ati pe Saulu ati awọn ọmọbibi rẹ̀ si kú, nwọn si fi ilu silẹ, nwọn si sa; awọn Filistini si wá, nwọn si joko si ilu wọn. 8 O si ṣe, li ọjọ keji, nigbati awọn Filistini de lati bọ́ nkan ti mbẹ lara awọn ti o kú, nwọn si ri pe, Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta ṣubu li oke Gilboa, 9 Nwọn si ke ori rẹ̀, nwọn si bọ́ ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ lọ si ilẹ Filistini ka kiri, lati ma sọ ọ nigbangba ni ile oriṣa wọn, ati larin awọn enia. 10 Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ si ile Aṣtaroti: nwọn si kàn okú rẹ̀ mọ odi Betṣani. 11 Nigbati awọn ara Jabeṣi-Gileadi si gbọ́ eyiti awọn Filistini ṣe si Saulu; 12 Gbogbo awọn ọkunrin alagbara si dide, nwọn si fi gbogbo oru na rìn, nwọn si gbe okú Saulu, ati okú awọn ọmọbibi rẹ̀ kuro lara odi Betṣani, nwọn si wá si Jabeṣi, nwọn si sun wọn nibẹ. 13 Nwọn si ko egungun wọn, nwọn si sin wọn li abẹ igi kan ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.

2 Samueli 1

Dafidi Gbọ́ nípa Ikú Saulu

1 O si ṣe lẹhin ikú Saulu, Dafidi si ti ibi iparun awọn ara Amaleki bọ̀, Dafidi si joko nijọ meji ni Siklagi; 2 O si ṣe ni ijọ kẹta, si wõ, ọkunrin kan si ti ibudo wá lati ọdọ Saulu; aṣọ rẹ̀ si faya, erupẹ si mbẹ li ori rẹ̀: o si ṣe, nigbati on si de ọdọ Dafidi, o wolẹ, o si tẹriba. 3 Dafidi si bi i lere pe, Nibo ni iwọ ti wá? o si wi fun u pe, Lati ibudo Israeli li emi ti sa wá. 4 Dafidi si tun bi lere wipe, Ọràn na ti ri? emi bẹ ọ, sọ fun mi. On si dahun pe, Awọn enia na sa loju ijà, ọ̀pọlọpọ ninu awọn enia na pẹlu si ṣubu; nwọn si kú, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ si kú pẹlu. 5 Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o sọ fun u lere pe, Iwọ ti ṣe mọ̀ pe, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ kú? 6 Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan. 7 Nigbati o si yi oju wo ẹhin rẹ̀, ti o si ri mi, o pè mi, Emi si da a lohùn pe, Emi nĩ. 8 On si bi mi pe, Iwọ tani? Emi si da a lohùn pe, ara Amaleki li emi. 9 On si tun wi fun mi pe, Duro le mi, emi bẹ ọ ki o si pa mi: nitoriti wahala ba mi, ẹmi mi si wà sibẹ. 10 Emi si duro le e, mo si pa a, nitori ti o da mi loju pe, kò si tun le là mọ lẹhin igbati o ti ṣubu: emi si mu ade ti o wà li ori rẹ̀, ati ibọwọ ti o mbẹ li apa rẹ̀, emi si mu wọn wá ihinyi sọdọ oluwa mi. 11 Dafidi si di aṣọ rẹ̀ mu, o si fà wọn ya, gbogbo awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀ si ṣe bẹ̃ gẹgẹ. 12 Nwọn si ṣọfọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbawẹ titi di aṣalẹ fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoripe nwọn ti ipa idà ṣubu. 13 Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o rò fun u wipe, Nibo ni iwọ ti wá? On si da a li ohùn pe, Ọmọ alejo kan, ara Amaleki li emi iṣe. 14 Dafidi si wi fun u pe, E ti ri ti iwọ kò fi bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo Oluwa? 15 Dafidi si pe ọkan ninu awọn ọmọdekunrin, o si wipe, Sunmọ ọ, ki o si kọ lu u. O si kọ lu u, on si kú. 16 Dafidi si wi fun u pe Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo Oluwa.

Orin Arò tí Dafidi kọ fún Saulu ati Jonatani

17 Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀: 18 O si pa aṣẹ lati kọ́ awọn ọmọ Juda ni ilò ọrun: wõ, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri. 19 Ẹwà rẹ Israeli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu! 20 Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si ṣe kokiki rẹ̀ ni igboro Aṣkeloni; ki awọn ọmọbinrin Filistini ki o má ba yọ̀, ki ọmọbinrin awọn alaikọla ki o má ba yọ̀. 21 Ẹnyin oke Gilboa, ki ìri ki o má si, ati ki ojò ki o má rọ̀ si nyin, ki ẹ má si ni oko ọrẹ ẹbọ: nitori nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a ko fi ororo yàn a. 22 Ọrun Jonatani ki ipada, ati idà Saulu ki ipada lasan lai kan ẹjẹ awọn ti a pa, ati ọra awọn alagbara. 23 Saulu ati Jonatani ni ifẹni si ara wọn, nwọn si dùn li ọjọ aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò ya ara wọn: nwọn yara ju idì lọ, nwọn si li agbara ju kiniun lọ. 24 Ẹnyin ọmọbinrin Israeli, ẹ sọkun lori Saulu, ti o fi aṣọ òdodó ati ohun ọṣọ́ wọ̀ nyin, ti o fi ohun ọṣọ́ wura si ara aṣọ nyin. 25 Wo bi awọn alagbara ti ṣubu larin ogun! A Jonatani! iwọ ti a pa li oke giga rẹ! 26 Wahala ba mi nitori rẹ, Jonatani, arakunrin mi: didùn jọjọ ni iwọ jẹ fun mi: ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o jù ifẹ obinrin lọ. 27 Wo bi awọn alagbara ti ṣubu, ati bi ohun ija ti ṣegbe!

2 Samueli 2

Wọ́n fi Dafidi Jọba Juda

1 O si ṣe lẹhin eyi, Dafidi si bere lọwọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke lọ si ọkan ni ilu Juda wọnni bi? Oluwa si wi fun u pe, Goke lọ: Dafidi si wipe, niha ibo ni ki emi ki o lọ? On si wipe, Ni Hebroni. 2 Dafidi si goke lọ si ibẹ ati awọn obinrin rẹ̀ mejeji pẹlu, Ahinoamu ara Jesreeli ati Abigaili obinrin Nabali ara Karmeli. 3 Dafidi si mu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ goke, olukuluku ton ti ara ile rẹ̀: nwọn si joko ni ilu Hebroni wọnni. 4 Awọn ọkunrin Juda si wá, nwọn si fi Dafidi jọba nibẹ lori ile Juda. Nwọn si sọ fun Dafidi pe, Awọn ọkunrin Jabeṣi Gileadi li o sinkú Saulu. 5 Dafidi si ran onṣẹ si awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi o si wi fun wọn pe, Alabukun fun li ẹnyin lati ọwọ́ Oluwa wá, bi ẹnyin ti ṣe õre yi si oluwa nyin, si Saulu, ani ti ẹ fi sinkú rẹ̀. 6 Njẹ ki Oluwa ki o ṣe ore ati otitọ fun nyin: emi na yio si san ore yi fun nyin, nitori ti ẹnyin ṣe nkan yi. 7 Njẹ ẹ si mu ọwọ́ nyin le, ki ẹ si jẹ ẹni-alagbara: nitoripe Saulu oluwa nyin ti kú, ile Juda si ti fi àmi-ororo yàn mi li ọba wọn.

Wọ́n fi Iṣiboṣẹti jọba Israẹli

8 Ṣugbọn Abneri ọmọ Neri olori ogun Saulu si mu Iṣboṣeti ọmọ Saulu, o si mu u kọja si Mahanaimu; 9 On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli. 10 Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jẹ ẹni ogoji ọdun nigbati o bẹrẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba li ọdun meji. Ṣugbọn idile Juda ntọ̀ Dafidi lẹhin. 11 Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba ni Hebroni lori ile Juda jẹ ọdun meje pẹlu oṣù mẹfa. 12 Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni. 13 Joabu ọmọ Seruia, ati awọn iranṣẹ Dafidi si jade, nwọn si jọ pade nibi adagun Gibeoni: nwọn si joko, ẹgbẹ kan li apa ihin adagun, ẹgbẹ keji li apa keji adagun. 14 Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ta pọrọ́ niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki wọn ki o dide. 15 Nigbana li awọn mejila ninu ẹya Benjamini ti iṣe ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu dide, nwọn si kọja siha keji; mejila ninu awọn ọmọ Dafidi si dide. 16 Olukuluku wọn si di ọmọnikeji rẹ̀ li ori mu, olukuluku si tẹ idà rẹ̀ bọ ẹnikeji rẹ̀ ni ihà: nwọn si jọ ṣubu lulẹ: nitorina li a si ṣe npe orukọ ibẹ na ni Helkatihassurimu, ti o wà ni Gibeoni. 17 Ijà na si kan gidigidi ni ijọ na, a si le Abneri ati awọn ọkunrin Israeli niwaju awọn ọmọ Dafidi. 18 Awọn ọmọ Seruia mẹtẹta si mbẹ nibẹ, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fẹrẹ bi ẹsẹ agbọnrin ti o wà ni pápa. 19 Asaheli si nlepa Abneri; bi on ti nlọ kò si yipada si ọwọ ọtun, tabi si ọwọ́ osì lati ma tọ Abneri lẹhin. 20 Nigbana ni Abneri boju wo ẹhin rẹ̀, o si bere pe, Iwọ Asaheli ni? On si dahùn pe, Emi ni. 21 Abneri si wi fun u pe, Iwọ yipada si apakan si ọwọ́ ọtun rẹ, tabi si osì rẹ, ki iwọ ki o si di ọkan mu ninu awọn ọmọkunrin, ki o si mu ihamọra rẹ̀. Ṣugbọn Asaheli kọ̀ lati pada lẹhin rẹ̀. 22 Abneri si tun wi fun Asaheli pe, Pada lẹhin mi, ẽṣe ti emi o fi lu ọ bolẹ? bawo li emi o ti ṣe gbe oju soke si Joabu arakunrin rẹ? 23 Ṣugbọn o si kọ̀ lati pada: Abneri si fi òdi ọ̀kọ gun u labẹ inu, ọ̀kọ na si jade li ẹhin rẹ̀: on si ṣubu lulẹ nibẹ, o si kú ni ibi kanna; o si ṣe, gbogbo enia ti o de ibiti Asaheli gbe ṣubu si, ti o si kú, si duro jẹ. 24 Joabu ati Abiṣai si lepa Abneri: õrun si wọ̀, nwọn si de oke ti Amma ti o wà niwaju Gia li ọ̀na iju Gibeoni. 25 Awọn ọmọ Benjamini si ko ara wọn jọ nwọn tẹle Abneri, nwọn si wa di ẹgbẹ kan, nwọn si duro lori oke kan. 26 Abneri si pe Joabu, o si bi i lere pe, Idà yio ma parun titi lailai bi? njẹ iwọ kò iti mọ̀ pe yio koro nikẹhin? njẹ yio ha ti pẹ to ki iwọ ki o to sọ fun awọn enia na, ki nwọn ki o dẹkun lati ma lepa ará wọn? 27 Joabu si wipe, Bi Ọlọrun ti mbẹ, bikoṣe bi iwọ ti wi, nitotọ, li owurọ̀ li awọn enia na iba ti goke lọ, olukuluku iba ti pada lẹhin arakunrin rẹ̀. 28 Joabu si fún ipè, gbogbo enia si duro jẹ, nwọn kò si lepa Israeli mọ, bẹ̃ni nwọn kò si tun jà mọ. 29 Abneri ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si fi gbogbo oru na rìn ni pẹtẹlẹ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si rìn ni gbogbo Bitroni, nwọn si wá si Mahanaimu. 30 Joabu si dẹkun ati ma tọ Abneri lẹhin: o si ko gbogbo awọn enia na jọ, enia mọkandi-logun li o kú pẹlu Asaheli ninu awọn iranṣẹ Dafidi. 31 Ṣugbọn awọn iranṣẹ Dafidi si lù bolẹ ninu awọn enia Benjamini; ati ninu awọn ọmọkunrin Abneri; ojì-di-ni-irin-wo enia li o kú. 32 Nwọn si gbe Asaheli, nwọn si sin i sinu ibojì baba rẹ̀ ti o wà ni Betlehemu. Joabu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ fi gbogbo oru na rin, ilẹ si mọ́ wọn si Hebroni.

2 Samueli 3

1 OGUN na si pẹ titi larin idile Saulu ati idile Dafidi: agbara Dafidi si npọ̀ si i, ṣugbọn idile Saulu nrẹ̀hin si i. 2 Dafidi si bi ọmọkunrin ni Hebroni: Ammoni li akọbi rẹ̀ ti Ahinoamu ara Jesreeli bi fun u. 3 Ekeji rẹ̀ si ni Kileabu, ti Abigaili aya Nabali ara Karmeli nì bi fun u; ẹkẹta si ni Absalomu ọmọ ti Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Geṣuri bi fun u. 4 Ẹkẹrin si ni Adonija ọmọ Haggiti; ati ikarun ni Ṣefatia ọmọ Abitali; 5 Ẹkẹfa si ni Itreamu, ti Egla aya Dafidi bi fun u. Wọnyi li a bi fun Dafidi ni Hebroni.

Abineri darapọ̀ mọ́ Dafidi

6 O si ṣe, nigbati ogun wà larin idile Saulu ati idile Dafidi, Abneri si di alagbara ni idile Saulu. 7 Saulu ti ni àle kan, orukọ rẹ̀ si njẹ Rispa, ọmọbinrin Aia: Iṣboṣeti si bi Abneri lere pe, Ẽṣe ti iwọ fi wọle tọ àle baba mi lọ? 8 Abneri si binu gidigidi nitori ọ̀rọ wọnyi ti Iṣboṣeti sọ fun u, o si wipe, Emi iṣe ori aja bi? emi ti mo mba Juda jà, ti mo si ṣanu loni fun idile Saulu baba rẹ, ati fun ará rẹ̀, ati awọn ọrẹ rẹ̀, ti emi kò si fi iwọ le Dafidi lọwọ, iwọ si ka ẹ̀ṣẹ si mi lọrùn nitori obinrin yi loni? 9 Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si Abneri, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi Oluwa ti bura fun Dafidi, bi emi kò ni ṣe bẹ fun u. 10 Lati mu ijọba na kuro ni idile Saulu, ati lati gbe itẹ Dafidi kalẹ lori Israeli, ati lori Juda, lati Dani titi o fi de Beerṣeba. 11 On kò si le da Abneri lohùn kan nitoriti o bẹ̀ru rẹ̀. 12 Abneri si ran awọn oniṣẹ si Dafidi nitori rẹ̀, wipe, Ti tani ilẹ na iṣe? ati pe, Ba mi ṣe adehun, si wõ, ọwọ́ mi o wà pẹlu rẹ, lati yi gbogbo Israeli sọdọ rẹ. 13 On si wi pe, O dara, emi o ba ọ ṣe adehun: ṣugbọn nkan kan li emi o bere lọwọ rẹ, eyini ni, Iwọ ki yio ri oju mi, afi bi iwọ ba mu Mikali ọmọbinrin Saulu wá, nigbati iwọ ba mbọ, lati ri oju mi. 14 Dafidi si ran awọn iranṣẹ si Iṣboṣeti ọmọ Saulu pe, Fi Mikali obinrin mi le mi lọwọ, ẹniti emi ti fi ọgọrun ẹfa abẹ awọn Filistini fẹ. 15 Iṣboṣeti si ranṣẹ, o si gbà a lọwọ ọkunrin ti a npè ni Faltieli ọmọ Laiṣi. 16 Ọkọ rẹ̀ si mba a lọ, o nrin, o si nsọkun lẹhin rẹ̀ titi o fi de Bahurimu. Abneri si wi fun u pe, Pada lọ. On si pada. 17 Abneri si ba awọn agbà Israeli sọ̀rọ, pe, Ẹnyin ti nṣe afẹri Dafidi ni igbà atijọ́, lati jọba lori nyin. 18 Njẹ, ẹ ṣe e: nitoriti Oluwa ti sọ fun Dafidi pe, Lati ọwọ́ Dafidi iranṣẹ mi li emi o gbà Israeli enia mi là kuro lọwọ awọn Filistini ati lọwọ gbogbo awọn ọta wọn. 19 Abneri si wi leti Benjamini: Abneri si lọ isọ leti Dafidi ni Hebroni gbogbo eyiti o dara loju Israeli, ati loju gbogbo ile Benjamini. 20 Abneri si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, ogún ọmọkunrin si pẹlu rẹ̀. Dafidi si se ase fun Abneri ati fun awọn ọmọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀. 21 Abneri si wi fun Dafidi pe, Emi o dide, emi o si lọ, emi o si ko gbogbo Israeli jọ sọdọ ọba oluwa mi, nwọn o si ba ọ ṣe adehun, iwọ o si jọba gbogbo wọn bi ọkàn rẹ ti nfẹ. Dafidi si rán Abneri lọ; on si lọ li alafia.

Wọ́n pa Abineri

22 Si wõ, awọn iranṣẹ Dafidi ati Joabu si ti ibi ilepa ẹgbẹ ogun kan bọ̀, nwọn si mu ikogun pupọ bọ̀; ṣugbọn Abneri ko si lọdọ Dafidi ni Hebroni; nitoriti on ti rán a lọ: on si ti lọ li alafia. 23 Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia. 24 Joabu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Kini iwọ ṣe nì? wõ, Abneri tọ̀ ọ wá; ehatiṣe ti iwọ si fi rán a lọ? on si ti lọ. 25 Iwọ mọ̀ Abneri ọmọ Neri, pe, o wá lati tàn ọ jẹ, ati lati mọ̀ ijadelọ rẹ, ati ibọsile rẹ, ati lati mọ̀ gbogbo eyi ti iwọ nṣe. 26 Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀. 27 Abneri si pada si Hebroni, Joabu si ba a tẹ̀ larin oju ọ̀na lati ba a sọ̀rọ li alafia, o si gún u nibẹ labẹ inu, o si kú, nitori ẹjẹ Asaheli arakunrin rẹ̀. 28 Lẹhin igbati Dafidi si gbọ́ ọ, o si wipe, emi ati ijọba mi si jẹ alaiṣẹ niwaju Oluwa titi lai ni ẹjẹ Abneri ọmọ Neri: 29 Jẹ ki o wà li ori Joabu, ati li ori gbogbo idile baba rẹ̀; ki a má si fẹ ẹni ti o li arùn isun, tabi adẹtẹ, tabi ẹni ti ntẹ̀ ọpá, tabi, ẹniti a o fi idà pa, tabi ẹniti o ṣe alaili onjẹ kù ni ile Joabu. 30 Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si pa Abneri, nitoripe on ti pa Asaheli arakunrin wọn ni Gibeoni li ogun.

Wọ́n Sin Òkú Abineri

31 Dafidi si wi fun Joabu ati fun gbogbo enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Ẹ fa aṣọ nyin ya, ki ẹnyin ki o si mu aṣọ-ọ̀fọ, ki ẹnyin ki o si sọkun niwaju Abneri. Dafidi ọba tikararẹ̀ si tẹle posi rẹ̀. 32 Nwọn si sin Abneri ni Hebroni: ọba si gbe ohùn rẹ̀ soke, o si sọkun ni iboji Abneri; gbogbo awọn enia na si sọkun. 33 Ọba si sọkun lori Abneri, o si wipe, Abneri iba ku iku aṣiwere? 34 A kò sa dè ọ li ọwọ́, bẹ̃ li a kò si kàn ẹsẹ rẹ li abà: gẹgẹ bi enia iti ṣubu niwaju awọn ikà enia, bẹ̃ni iwọ ṣubu. Gbogbo awọn enia na si tun sọkun lori rẹ̀. 35 Nigbati gbogbo enia si wá lati gbà Dafidi ni iyanju ki o jẹun nigbati ọjọ si mbẹ, Dafidi si bura wipe, Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati ju bẹ̃ lọ, bi emi ba tọ onjẹ wò, tabi nkan miran, titi õrun yio fi wọ̀. 36 Gbogbo awọn enia si kiyesi i, o si dara loju wọn: gbogbo eyi ti ọba ṣe si dara loju gbogbo awọn enia na. 37 Gbogbo awọn enia na ati gbogbo Israeli si mọ̀ lọjọ na pe, ki iṣe ifẹ ọba lati pa Abneri ọmọ Neri. 38 Ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin kò mọ̀ pe olori ati ẹni-nla kan li o ṣubu li oni ni Israeli? 39 Emi si ṣe alailagbara loni, bi o tilẹ jẹ pe a fi emi jọba; awọn ọkunrin wọnyi ọmọ Seruia si le jù mi lọ: Oluwa ni yio san a fun ẹni ti o ṣe ibi gẹgẹ bi ìwa buburu rẹ̀.

2 Samueli 4

Wọ́n pa Iṣiboṣẹti

1 NIGBATI ọmọ Saulu si gbọ́ pe Abneri kú ni Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ si rọ, gbogbo Israeli si rẹ̀wẹsi. 2 Ọmọ Saulu si ni ọkunrin meji ti iṣe olori ẹgbẹ ogun: a npe orukọ ọkan ni Baana, ati orukọ keji ni Rekabu, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti ti awọn ọmọ Benjamini: (nitoripe a si ka Beeroti pẹlu Benjamini: 3 Awọn ara Beeroti si ti sa lọ si Gittaimu, nwọn si ṣe atipo nibẹ titi o fi di ọjọ oni yi.) 4 Jonatani ọmọ Saulu si ti bi ọmọkunrin kan ti ẹsẹ rẹ̀ rọ. On si jẹ ọdun marun, nigbati ihìn de niti Saulu ati Jonatani lati Jesreeli wá, olutọ́ rẹ̀ si gbe e, o si sa lọ: o si ṣe, bi o si ti nyara lati sa lọ, on si ṣubu, o si ya arọ. Orukọ rẹ̀ a ma jẹ Mefiboṣeti. 5 Awọn ọmọ Rimmoni, ara Beeroti, Rekabu ati Baana si lọ, nwọn si wá si ile Iṣboṣeti li ọsangangan, on si dubulẹ lori ibusun kan li ọjọkanri. 6 Si wõ, nwọn si wá si arin ile na, nwọn si ṣe bi ẹnipe nwọn nfẹ mu alikama; nwọn si gun u labẹ inu: Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀ si sa lọ. 7 Nigbati nwọn wọ ile na lọ, on si dubulẹ lori ibusun rẹ̀ ninu iyẹwu rẹ̀, nwọn si lu u pa, nwọn si bẹ ẹ li ori, nwọn gbe ori rẹ̀, nwọn si fi gbogbo oru rìn ni pẹtẹlẹ na. 8 Nwọn si gbe ori Iṣboṣeti tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wi fun ọba pe, Wõ, ori Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọta rẹ, ti o ti nwá ẹmi rẹ kiri; Oluwa ti gbẹ̀san fun ọba oluwa mi loni lara Saulu ati lara iru-ọmọ rẹ̀. 9 Dafidi si da Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti lohùn, o si wi fun wọn pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ẹniti o gbà ẹmi mi lọwọ gbogbo ipọnju, 10 Nigbati ẹnikan rò fun mi pe, Wõ, Saulu ti kú, li oju ara rẹ̀ on si jasi ẹni ti o mu ihin rere wá, emi si mu u, mo si pa a ni Siklagi, ẹniti o ṣebi on o ri nkan gbà nitori ihin rere rẹ̀. 11 Melomelo ni, nigbati awọn ikà enia pa olododo enia kan ni ile rẹ̀ lori ibusun rẹ̀? njẹ emi ha si le ṣe alaibere ẹjẹ rẹ̀ lọwọ nyin bi? ki emi si mu nyin kuro laiye? 12 Dafidi si fi aṣẹ fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, nwọn si pa wọn, nwọn si ke ọwọ́ ati ẹṣẹ wọn, a si fi wọn ha lori igi ni Hebroni. Ṣugbọn nwọn mu ori Iṣboṣeti, nwọn si sin i ni iboji Abneri ni Hebroni.

2 Samueli 5

Dafidi di Ọba Israẹli ati ti Juda

1 GBOGBO ẹya Israeli si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wipe, Wõ, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe. 2 Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli. 3 Gbogbo agba Israeli si tọ ọba wá ni Hebroni, Dafidi ọba si ba wọn ṣe adehun kan ni Hebroni, niwaju Oluwa: nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba Israeli. 4 Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun. 5 O jọba ni Hebroni li ọdun meje on oṣu mẹfa lori Juda: o si jọba ni Jerusalemu li ọdun mẹtalelọgbọn lori gbogbo Israeli ati Juda. 6 Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin. 7 Ṣugbọn Dafidi si fi agbara gbà ilu odi Sioni: eyi na ni iṣe ilu Dafidi. 8 Dafidi si sọ lọjọ na pe, Ẹnikẹni ti yio kọlu awọn ara Jebusi, jẹ ki o gbà oju àgbàrá, ki o si kọlu awọn arọ ati awọn afọju ti ọkàn Dafidi korira. Nitorina ni nwọn ṣe wipe, Afọju ati arọ wà nibẹ, kì yio le wọle. 9 Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀. 10 Dafidi si npọ̀ si i, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun si wà pẹlu rẹ̀. 11 Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi. 12 Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀. 13 Dafidi si tun mu awọn alè ati aya si i lati Jerusalemu wá, lẹhin igbati o ti Hebroni bọ̀: nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin fun Dafidi. 14 Eyi si ni orukọ awọn ti a bi fun u ni Jerusalemu, Ṣammua ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, 15 Ati Ibehari, ati Eliṣua, ati Nefegi, ati Jafia, 16 Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifaleti,

Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia

17 Ṣugbọn nigbati awọn Filistini gbọ́ pe, nwọn ti fi Dafidi jọba lori Israeli, gbogbo awọn Filistini si goke wá lati wa Dafidi; Dafidi si gbọ́, o si sọkalẹ lọ si ilu odi. 18 Awọn Filistini si wá, nwọn si tẹ́ ara wọn li afonifoji Refaimu. 19 Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ. 20 Dafidi si de Baal-perasimu, Dafidi si pa wọn nibẹ, o si wipe, Oluwa ti ya lù awọn ọtá mi niwaju mi, gẹgẹ bi omi iti ya. Nitorina li on ṣe pe orukọ ibẹ na ni Baal-perasimu. 21 Nwọn si fi oriṣa wọn silẹ nibẹ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si ko wọn. 22 Awọn Filistini si tún goke wá, nwọn si tàn ara wọn kalẹ ni afonifoji Refaimu. 23 Dafidi si bere lọdọ Oluwa, on si wipe, Máṣe goke lọ; ṣugbọn bù wọn lẹhin, ki o si kọlu wọn niwaju awọn igi Baka. 24 Yìo si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lori awọn igi Baka na, nigbana ni iwọ o si yara, nitoripe nigbana li Oluwa yio jade lọ niwaju rẹ, lati kọlu ogun awọn Filistini. 25 Dafidi si ṣe bẹ̃, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun u; o si kọlu awọn Filistini lati Geba titi o fi de Gaseri.

2 Samueli 6

Wọ́n Gbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sí Jerusalẹmu

1 DAFIDI si tun ko gbogbo awọn akọni ọkunrin ni Israeli jọ, nwọn si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun. 2 Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu. 3 Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na. 4 Nwọn si mu u lati ile Abinadabu jade wá, ti o wà ni Gibea, pẹlu apoti-ẹri Ọlọrun; Ahio si nrìn niwaju apoti-ẹri na. 5 Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro. 6 Nigbati nwọn si de ibi ipakà Nakoni, Ussa si nà ọwọ́ rẹ̀ si apoti-ẹri Ọlọrun, o si dì i mu, nitoriti malu kọsẹ. 7 Ibinu Oluwa si ru si Ussa; Ọlọrun si pa a nibẹ nitori iṣiṣe rẹ̀; nibẹ li o si kú li ẹba apoti-ẹri Ọlọrun. 8 Inu Dafidi si bajẹ nitoriti Oluwa ke Ussa kuro: o si pe orukọ ibẹ na ni Peresi-Ussa titi o fi di oni yi. 9 Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá? 10 Dafidi kò si fẹ mu apoti-ẹri Oluwa sọdọ rẹ̀ si ilu Dafidi: ṣugbọn Dafidi si mu u yà si ile Obedi-Edomu ara Gati. 11 Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀. 12 A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀. 13 O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ. 14 Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀. 15 Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè. 16 Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀. 17 Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa. 18 Dafidi si pari iṣẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na, o si sure fun awọn enia na li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun. 19 O si pin fun gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo ọpọ enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin; fun olukuluku iṣu akara kan ati ẹkirí ẹran kan, ati akara didun kan. Gbogbo awọn enia na si tuka lọ, olukuluku si ile rẹ̀. 20 Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ! 21 Dafidi si wi fun Mikali pe, Niwaju Oluwa ni, ẹniti o yàn mi fẹ jù baba rẹ lọ, ati ju gbogbo idile rẹ̀ lọ, lati fi emi ṣe olori awọn enia Oluwa, ani lori Israeli, emi o si ṣire niwaju Oluwa. 22 Emi o si tun rẹ̀ ara mi silẹ jù bẹ̃ lọ, emi o si ṣe alainiyìn loju ara mi, ati loju awọn iranṣẹbinrin wọnni ti iwọ wi, lọdọ wọn na li emi o si li ogo. 23 Mikali ọmọbinrin Saulu kò si bi ọmọ, titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀.

2 Samueli 7

Iṣẹ́ tí Natani jẹ́ fún Dafidi

1 O si ṣe, nigbati ọba si joko ni ile rẹ̀, ti Oluwa si fun u ni isimi yika kiri kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ̀. 2 Ọba si wi fun Natani woli pe, Sa wõ, emi ngbe inu ile ti a fi kedari kọ, ṣugbọn apoti-ẹri Ọlọrun ngbe inu ibi ti a fi aṣọ ke. 3 Natani si wi fun ọba pe, Lọ, ki o si ṣe gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ. 4 O si ṣe li oru na, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Natani wá, pe, 5 Lọ, sọ fun iranṣẹ mi, fun Dafidi, pe, Bayi li Oluwa wi, iwọ o ha kọ ile fun mi ti emi o gbe? 6 Nitoripe, emi ko iti gbe inu ile kan lati ọjọ ti emi ti mu awọn ọmọ Israeli goke ti ilẹ Egipti wá, titi di oni yi, ṣugbọn emi ti nrin ninu agọ, ati ninu agberin. 7 Ni ibi gbogbo ti emi ti nrin larin gbogbo awọn ọmọ Israeli, emi ko ti iba ọkan ninu ẹya Israeli, ti emi pa aṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi ani Israeli sọ̀rọ pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kedari kọ ile fun mi? 8 Njẹ, nitorina, bayi ni iwọ o si wi fun iranṣẹ mi ani Dafidi pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ti mu iwọ kuro lati inu agbo agutan wá, lati má mã tẹle awọn agutan, mo si fi ọ jẹ olori awọn enia mi, ani Israeli. 9 Emi si wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ nlọ, emi sa ke gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi si ti sọ orukọ rẹ di nla, gẹgẹ bi orukọ awọn enia nla ti o wà li aiye. 10 Emi o si yàn ibi kan fun awọn enia mi, ani Israeli, emi o si gbìn wọn, nwọn o si ma joko ni ibujoko ti wọn, nwọn kì yio si ṣipo pada mọ; awọn ọmọ enia buburu kì yio si pọn wọn loju mọ, bi igba atijọ. 11 Ati gẹgẹ bi akoko igba ti emi ti fi aṣẹ fun awọn onidajọ lori awọn enia mi, ani Israeli, emi fi isimi fun ọ lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ. Oluwa si wi fun ọ pe, Oluwa yio kọ ile kan fun ọ. 12 Nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o si sùn pẹlu awọn baba rẹ, emi o si gbe iru-ọmọ rẹ leke lẹhin rẹ, eyi ti o ti inu rẹ jade wá, emi o si fi idi ijọba rẹ kalẹ. 13 On o si kọ ile fun orukọ mi, emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ kalẹ lailai. 14 Emi o ma ṣe baba fun u, on o si ma jẹ ọmọ mi. Bi on ba dẹṣẹ, emi o si fi ọpá enia nà a, ati inà awọn ọmọ enia. 15 Ṣugbọn ãnu mi kì yio yipada kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu kuro niwaju rẹ. 16 A o si fi idile rẹ ati ijọba rẹ mulẹ niwaju rẹ titi lai: a o si fi idi itẹ rẹ mulẹ titi lai. 17 Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani si sọ fun Dafidi.

Adura Ọpẹ́ tí Dafidi Gbà

18 Dafidi ọba si wọle lọ, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun, tali emi, ati ki si ni idile mi, ti iwọ fi mu mi di isisiyi? 19 Nkan kekere li eyi sa jasi li oju rẹ, Oluwa Ọlọrun; iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina. Eyi ha ṣe ìwa enia bi, Oluwa Ọlọrun? 20 Kini Dafidi iba si ma wi si i fun ọ? Iwọ, Oluwa Ọlọrun mọ̀ iranṣẹ rẹ. 21 Nitori ọ̀rọ rẹ, ati gẹgẹ bi ifẹ ọkàn rẹ, ni iwọ ṣe gbogbo nkan nla wọnyi, ki iranṣẹ rẹ ki o le mọ̀. 22 Iwọ si tobi, Oluwa Ọlọrun: kò si si ẹniti o dabi rẹ, kò si si Ọlọrun kan lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa fi eti wa gbọ́. 23 Orilẹ-ède kan wo li o si mbẹ li aiye ti o dabi awọn enia rẹ, ani Israeli, awọn ti Ọlọrun lọ ràpada lati sọ wọn di enia rẹ̀, ati lati sọ wọn li orukọ, ati lati ṣe nkan nla fun nyin, ati nkan iyanu fun ilẹ rẹ, niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada fun ara rẹ lati Egipti wá, ani awọn orilẹ-ède ati awọn oriṣa wọn. 24 Iwọ si fi idi awọn enia rẹ, ani Israeli, kalẹ fun ara rẹ lati sọ wọn di enia rẹ titi lai: iwọ Oluwa si wa di Ọlọrun fun wọn. 25 Njẹ, Oluwa Ọlọrun, jẹ ki ọ̀rọ na ti iwọ sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti idile rẹ̀, ki o duro titi lai, ki o si ṣe bi iwọ ti wi. 26 Jẹ ki orukọ rẹ ki o ga titi lai, pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li Ọlọrun lori Israeli: si jẹ ki a fi idile Dafidi iranṣẹ rẹ mulẹ niwaju rẹ. 27 Nitoripe iwọ, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli ti sọ li eti iranṣẹ rẹ, pe, emi o ṣe idile kan fun ọ: nitorina ni iranṣẹ rẹ si ṣe ni i li ọkàn rẹ̀ lati gbadura yi si ọ. 28 Njẹ, Oluwa Ọlọrun, iwọ li Ọlọrun na, ọrọ rẹ wọnni yio si jasi otitọ, iwọ si jẹ'jẹ nkan rere yi fun iranṣẹ rẹ: 29 Njẹ, jẹ ki o wù ọ lati bukún idile iranṣẹ rẹ, ki o wà titi lai niwaju rẹ: nitori iwọ, Oluwa Ọlọrun, li o ti sọ ọ: si jẹ ki ibukún ki o wà ni idile iranṣẹ rẹ titi lai, nipasẹ ibukún rẹ.

2 Samueli 8

Àwọn Ogun tí Dafidi jà ní àjàṣẹ́gun

1 O SI ṣe, lẹhin eyi, Dafidi si kọlu awọn Filistini, o si tẹri wọn ba: Dafidi si gbà Metegamma lọwọ awọn Filistini. 2 O si kọlu Moabu, a si fi okùn tita kan diwọ̀n wọn, o si da wọn bu'lẹ; o si ṣe oṣuwọn okun meji ni iye awọn ti on o pa, ati ẹkún oṣuwọn okùn kan ni iye awọn ti yio dá si. Awọn ara Moabu si nsìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. 3 Dafidi si kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bi on si ti nlọ lati gbà ilẹ rẹ̀ pada ti o gbè odo Eufrate. 4 Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ lọwọ rẹ̀, ati ẹ̃dẹgbẹrin ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa awọn ẹlẹsẹ: Dafidi si ja gbogbo ẹṣin kẹkẹ́ wọn wọnni ni pátì, ṣugbọn o da ọgọrun kẹkẹ́ si ninu wọn. 5 Nigbati awọn ara Siria ti Damasku si wá lati ran Hadadeseri ọba Soba lọwọ, Dafidi si pa ẹgbãmọkanla enia ninu awọn ara Siria. 6 Dafidi si fi awọn ologun si Siria ti Damasku: awọn ara Siria si wa sìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ. 7 Dafidi si gbà aṣà wura ti o wà lara awọn iranṣẹ Hadadeseri, o si ko wọn wá si Jerusalemu. 8 Lati Beta, ati lati Berotai, awọn ilú Hadadeseri, ni Dafidi ọba si ko ọ̀pọlọpọ idẹ wá. 9 Nigbati Toi ọba Hamati si gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri, 10 Toi si ran Joramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba, lati ki i, ati lati sure fun u, nitoripe o ti ba Hadadeseri jagun, o si ti pa a: nitoriti Hadadeseri sa ti ba Toi jagun. Joramu si ni ohun elo fadaka, ati ohun elo wura, ati ohun elo idẹ li ọwọ́ rẹ̀: 11 Dafidi ọba si fi wọn fun Oluwa, pẹlu fadaka, ati wura ti o ti yà si mimọ́, eyi ti o ti gbà lọwọ awọn orilẹ-ède ti o ti ṣẹgun; 12 Lọwọ Siria ati lọwọ Moabu, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini, ati lọwọ Amaleki, ati ninu ikogun Hadadeseri ọmọ Rehobu ọba Soba. 13 Dafidi si ni asiki gidigidi nigbati o pada wá ile lati ibi pipa awọn ara Siria li afonifoji iyọ̀, awọn ti o pa jẹ ẹgbãsan enia. 14 O si fi awọn ologun si Edomu; ati ni gbogbo Edomu yika li on si fi ologun si, gbogbo awọn ti o wà ni Edomu si wá sin Dafidi. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ. 15 Dafidi si jọba lori gbogbo Israeli; Dafidi si ṣe idajọ ati otitọ fun awọn enia rẹ̀. 16 Joabu ọmọ Seruia li o si nṣe olori ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si nṣe akọwe. 17 Ati Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; Seruia a si ma ṣe akọwe. 18 Benaiah ọmọ Jehoiada li o si nṣe olori awọn Kereti, ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si jẹ alaṣẹ.

2 Samueli 9

Dafidi ati Mẹfiboṣẹti

1 DAFIDI si bere pe, ọkan ninu awọn ẹniti iṣe idile Saulu kù sibẹ bi? ki emi ki o le ṣe ore fun u nitori Jonatani. 2 Iranṣẹ kan si ti wà ni idile Saulu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Siba. Nwọn si pè e wá sọdọ Dafidi, ọba si bere lọwọ rẹ̀ pe, Iwọ ni Siba bi? O si dahùn wipe, Iranṣẹ rẹ ni. 3 Ọba si wipe, Kò ha si ọkan ninu idile Saulu sibẹ, ki emi ki o ṣe ore Ọlọrun fun u? Siba si wi fun ọba pe, Jonatani ní ọmọ kan sibẹ ti o ya arọ. 4 Ọba si wi fun u pe, Nibo li o gbe wà? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, on wà ni ile Makiri, ọmọ Ammieli, ni Lodebari. 5 Dafidi ọba si ranṣẹ, o si mu u lati ile Makiri ọmọ Ammieli lati Lodebari wá. 6 Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu si tọ̀ Dafidi wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si bu ọla fun u. Dafidi si wipe, Mefiboṣeti. On si dahùn wipe, Wo iranṣẹ rẹ! 7 Dafidi si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. 8 On si tẹriba, o si wipe, Kini iranṣẹ rẹ jasi, ti iwọ o fi ma wo okú aja bi emi? 9 Ọba si pe Siba iranṣẹ Saulu, o si wi fun u pe, Gbogbo nkan ti iṣe ti Saulu, ati gbogbo eyi ti iṣe ti idile rẹ̀ li emi fi fun ọmọ oluwa rẹ. 10 Iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ ni yio si ma ro ilẹ na fun u, iwọ ni yio si ma mu ikore wá, ọmọ oluwa rẹ yio si ma ri onjẹ jẹ: ṣugbọn Mefiboṣeti ọmọ oluwa rẹ̀ yio si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. Siba si ni ọmọ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹkunrin. 11 Siba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti pa li aṣẹ fun iranṣẹ rẹ, bẹ̃na ni iranṣẹ rẹ o si ṣe. Ọba si wi pe, Niti Mefiboṣeti, yio ma jẹun ni ibi onjẹ mi, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ ọba. 12 Mefiboṣeti si ni ọmọ kekere kan, orukọ rẹ̀ njẹ Mika. Gbogbo awọn ti ngbe ni ile Siba li o si nṣe iranṣẹ fun Mefiboṣeti. 13 Mefiboṣeti si ngbe ni Jerusalemu: on a si ma jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ ọba; on si yarọ li ẹsẹ rẹ̀ mejeji.

2 Samueli 10

Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni ati Àwọn Ará Siria

1 O si ṣe lẹhin eyi, ọba awọn ọmọ Ammoni si kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. 2 Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹgẹ bi baba rẹ̀ si ti ṣe ore fun mi. Dafidi si ranṣẹ lati tù u ninu lati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀ wá, nitori ti baba rẹ̀. Awọn iranṣẹ Dafidi si wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni. 3 Awọn olori awọn ọmọ Ammoni si wi fun Hanuni oluwa wọn pe, Li oju rẹ, ọlá ni Dafidi mbù fun baba rẹ, ti o fi ran awọn olutùnú si ọ? ko ha se pe, Dafidi ran awọn iranṣẹ rẹ̀ si ọ, lati wa wò ilu, ati lati ṣe alami rẹ̀, ati lati bà a jẹ? 4 Hanuni si mu awọn iranṣẹ Dafidi, o fá apakan irungbọ̀n wọn, o si ke abọ̀ kuro ni agbáda wọn, titi o fi de idi wọn, o si rán wọn lọ. 5 Nwọn si sọ fun Dafidi, o si ranṣẹ lọ ipade wọn, nitoriti oju tì awọn ọkunrin na pupọ̀: ọba si wipe. Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọ̀n nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ padà bọ̀. 6 Awọn ọmọ Ammoni si ri pe, nwọn di ẹni irira niwaju Dafidi, awọn ọmọ Ammoni si ranṣẹ, nwọn si fi owo bẹ̀ ogun awọn ara Siria ti Betrehobu; ati Siria ti Soba, ẹgbãwa ẹlẹsẹ ati ti ọba Maaka, ẹgbẹrun ọkunrin, ati ti Iṣtobu ẹgbãfa ọkunrin. 7 Dafidi si gbọ́, o si rán Joabu, ati gbogbo ogun awọn ọkunrin alagbara. 8 Awọn ọmọ Ammoni si jade, nwọn si tẹ́ ogun li ẹnu odi; ara Siria ti Soba, ati ti Rehobu, ati Iṣtobu, ati Maaka, nwọn si tẹ́ ogun ni papa fun ara wọn. 9 Nigbati Joabu si ri i pe ogun na doju kọ on niwaju ati lẹhin, o si yàn ninu gbogbo awọn akikanju ọkunrin ni Israeli, o si tẹ́ ogun kọju si awọn ara Siria. 10 O si fi awọn enia ti o kù le Abiṣai aburo rẹ̀ lọwọ, ki o le tẹ́ ogun kọju si awọn ọmọ Ammoni. 11 O si wipe, Bi agbara awọn ara Siria ba si pọ̀ jù emi lọ, iwọ o si wá ràn mi lọwọ: ṣugbọn bi ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni ba si pọ̀ jù ọ lọ, emi o si wá ràn ọ lọwọ. 12 Mu ọkàn le, jẹ ki a ṣe onigboya nitori awọn enia wa, ati nitori awọn ilu Ọlọrun wa; Oluwa o si ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀. 13 Joabu ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si ba awọn ara Siria pade ijà: nwọn si sa niwaju rẹ̀. 14 Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn si sá niwaju Abiṣai, nwọn si wọ inu ilu lọ. Joabu si pada kuro lẹhin awọn ọmọ Ammoni, o si pada wá si Jerusalemu. 15 Nigbati awọn ara Siria si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ko ara wọn jọ. 16 Hadareseri si ranṣẹ, o si mu awọn ara Siria ti o wà li oke odo jade wá: nwọn si wá si Helami; Ṣobaki olori ogun ti Hadareseri si ṣolori wọn. 17 Nigbati a sọ fun Dafidi, o si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si wá si Helami. Awọn ara Siria si tẹ́ ogun kọju si Dafidi, nwọn si ba a jà. 18 Awọn ara Siria si sa niwaju Israeli; Dafidi si pa ninu awọn ara Siria ẽdẹgbẹrin awọn onikẹkẹ́, ati ọkẹ meji ẹlẹṣin, nwọn si kọlu Ṣobaki olori ogun wọn, o si kú nibẹ. 19 Nigbati gbogbo awọn ọba ti o wà labẹ Hadareseri si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ba Israeli lajà, nwọn si nsìn wọn. Awọn ara Siria si bẹ̀ru lati ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.

2 Samueli 11

Dafidi ati Batiṣeba

1 O si ṣe, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima jade ogun, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si dó ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalemu. 2 O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò. 3 Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti? 4 Dafidi si rán awọn iranṣẹ, o si mu u; on si wọ inu ile tọ̀ ọ lọ, on si ba a dapọ̀: nigbati o si wẹ ara rẹ̀ mọ́ tan, o si pada lọ si ile rẹ̀. 5 Obinrin na si fẹra kù, o si ranṣẹ o si sọ fun Dafidi, o si wipe, Emi fẹra kù. 6 Dafidi si ranṣẹ si Joabu, pe, Ran Uria ará Hitti si mi. Joabu si ran Uria si Dafidi. 7 Nigbati Uria si de ọdọ rẹ̀, Dafidi si bi i li ere alafia Joabu, ati alafia awọn enia na, ati bi ogun na ti nṣe. 8 Dafidi si wi fun Uria pe, Sọkalẹ lọ si ile rẹ, ki o si wẹ ẹsẹ rẹ. Uria si jade kuro ni ile ọba, onjẹ lati ọdọ ọba wá si tọ̀ ọ lẹhin. 9 Ṣugbọn Uria sùn li ẹnu-ọ̀na ile ọba lọdọ gbogbo iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀. 10 Nigbati nwọn si sọ fun Dafidi pe, Uria kò sọkalẹ lọ si ile rẹ̀, Dafidi si wi fun Uria pe, Ṣe ọ̀na àjo ni iwọ ti wá? eha ti ṣe ti iwọ kò fi sọkalẹ lọ si ile rẹ? 11 Uria si wi fun Dafidi pe, Apoti-ẹri, ati Israeli, ati Juda joko ninu agọ; ati Joabu oluwa mi, ati awọn iranṣẹ oluwa mi wà ni ibudo ni pápa: emi o ha lọ si ile mi, lati jẹ ati lati mu, ati lati ba obinrin mi sùn? bi iwọ ba wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti mbẹ lãye, emi kì yio ṣe nkan yi. 12 Dafidi si wi fun Uria pe, Si duro nihin loni, li ọla emi o si jẹ ki iwọ ki o lọ. Uria si duro ni Jerusalemu li ọjọ na, ati ijọ keji. 13 Dafidi si pè e, o si jẹ, o si mu niwaju rẹ̀; o si mu ki ọti ki o pa a: on si jade li alẹ lọ si ibusùn rẹ̀ lọdọ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀. 14 O si ṣe li owurọ Dafidi si kọwe si Joabu, o fi rán Uria. 15 O si kọ sinu iwe pe, Fi Uria siwaju ibi tí ogun gbe le, ki ẹ si bó o silẹ, ki nwọn le kọ lù u, ki o si kú. 16 O si ṣe nigbati Joabu ṣe akiyesi ilu na, o si yàn Uria si ibi kan ni ibi ti on mọ̀ pe awọn alagbara ọkunrin mbẹ nibẹ. 17 Awọn ọkunrin ilu na si jade wá, nwọn si ba Joabu jà: diẹ si ṣubu ninu awọn enia na ninu awọn iranṣẹ Dafidi; Uria ará Hitti si kú pẹlu. 18 Joabu si ranṣẹ o si rò gbogbo nkan ogun na fun Dafidi. 19 O si paṣẹ fun iranṣẹ na pe, Nigbati iwọ ba si pari ati ma rò gbogbo nkan ogun na fun ọba, 20 Bi o ba ṣe pe, ibinu ọba ba fàru, ti on si wi fun ọ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sunmọ ilu na lati ba wọn jà, ẹnyin kò mọ̀ pe nwọn o tafà lati ori odi wá? 21 Tali o pa Abimeleki ọmọ Jerubbeṣeti? Ki iṣe obinrin li o yi okuta ọlọ lù u lati ori odi wá, ti o si kú ni Tebeṣi? ẽha ti ri ti ẹnyin fi sunmọ odi na? Iwọ o si wi fun u pe, Uria iranṣẹ rẹ ará Hitti kú pẹlu. 22 Iranṣẹ na si lọ, o si wá, o si jẹ gbogbo iṣẹ ti Joabu ran a fun Dafidi. 23 Iranṣẹ na si wi fun Dafidi pe, Nitõtọ awọn ọkunrin na lagbara jù wa lọ, nwọn si jade tọ̀ wa wá ni pápa, awa si tẹle wọn titi nwọn fi de ẹhìn odi. 24 Awọn tafàtafa si ta si iranṣẹ rẹ lati ori odi wá, diẹ ninu awọn iranṣẹ ọba si kú, iranṣẹ rẹ Uria ará Hitti si kú pẹlu. 25 Dafidi si wi fun iranṣẹ na pe, Bayi ni iwọ o wi fun Joabu pe, Máṣe jẹ ki nkan yi ki o buru li oju rẹ, nitoripe idà a ma jẹ li ọtun li òsi, mu ijà rẹ le si ilu na, ki o si bì i ṣubu: ki iwọ ki o si mu u lọkàn le. 26 Nigbati aya Uria si gbọ́ pe Uria ọkọ rẹ̀ kú, o si gbawẹ̀ nitori ọkọ rẹ̀. 27 Nigbati awẹ̀ na si kọja tan, Dafidi si ranṣẹ, o si mu u wá si ile rẹ̀, on si wa di aya rẹ̀, o si bi ọmọkunrin kan fun u. Ṣugbọn nkan na ti Dafidi ṣe buru niwaju Oluwa.

2 Samueli 12

Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ ati Ìrònúpìwàdà Dafidi

1 OLUWA si ran Natani si Dafidi. On si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Ọkunrin meji mbẹ ni ilu kan; ọkan jẹ ọlọrọ̀, ekeji si jẹ talaka. 2 Ọkunrin ọlọrọ̀ na si ni agutan ati malu li ọ̀pọlọpọ, 3 Ṣugbọn ọkunrin talaka na kò si ni nkan, bikoṣe agutan kekere kan, eyi ti o ti rà ti o si ntọ́: o si dagba li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀; a ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀, a si ma mu ninu ago rẹ̀, a si ma dubulẹ li aiya rẹ̀, o si dabi ọmọbinrin kan fun u. 4 Alejo kan si tọ̀ ọkunrin ọlọrọ̀ na wá, on kò si fẹ mu ninu agutàn rẹ̀, ati ninu malu rẹ̀, lati fi ṣe alejo fun ẹni ti o tọ̀ ọ wá: o si mu agutan ọkunrin talaka na fi ṣe alejo fun ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá. 5 Ibinu Dafidi si fàru gidigidi si ọkunrin na; o si wi fun Natani pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkunrin na ti o ṣe nkan yi, kikú ni yio kú. 6 On o si san agutan na pada ni ìlọ́po mẹrin, nitoriti o ṣe nkan yi, ati nitoriti kò ni ãnu. 7 Natani si wi fun Dafidi pe, Iwọ li ọkunrin na. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi fi ọ jọba lori Israeli, emi si gbà ọ lọwọ Saulu; 8 Emi si fi ile oluwa rẹ fun ọ, ati awọn obinrin oluwa rẹ si aiyà rẹ, emi si fi idile Israeli ati ti Juda fun ọ; iba tilẹ ṣepe eyini kere jù, emi iba si fun ọ ni nkan bayi bayi. 9 Eṣe ti iwọ fi kẹgàn ọ̀rọ Oluwa, ti iwọ fi ṣe nkan ti o buru li oju rẹ̀, ani ti iwọ fi fi idà pa Uria ará Hitti, ati ti iwọ fi mu obinrin rẹ̀ lati fi ṣe obinrin rẹ, o si fi idà awọn ọmọ Ammoni pa a. 10 Njẹ nitorina idà kì yio kuro ni ile rẹ titi lai; nitoripe iwọ gàn mi, iwọ si mu aya Uria ará Hitti lati fi ṣe aya rẹ. 11 Bayi li Oluwa wi, Kiye si i, Emi o jẹ ki ibi ki o dide si ọ lati inu ile rẹ wá, emi o si gbà awọn obinrin rẹ loju rẹ, emi o si fi wọn fun aladugbo rẹ, on o si ba awọn obinrin rẹ sùn niwaju õrun yi. 12 Ati pe iwọ ṣe e ni ikọ̀kọ: ṣugbọn emi o ṣe nkan yi niwaju gbogbo Israeli, ati niwaju õrun. 13 Dafidi si wi fun Natani pe, Emi ṣẹ̀ si Oluwa. Natani si wi fun Dafidi pe, Oluwa pẹlu si ti mu ẹ̀ṣẹ rẹ kuro; iwọ kì yio kú. 14 Ṣugbọn nitori nipa iwa yi, iwọ fi aye silẹ fun awọn ọta Oluwa lati sọ ọ̀rọ òdi, ọmọ na ti a o bi fun ọ, kiku ni yio ku. 15 Natani si lọ si ile rẹ̀. Oluwa si fi arùn kọlù ọmọ na ti obinrin Uria bi fun Dafidi, o si ṣe aisàn pupọ.

Ọmọ Dafidi Ṣàìsí

16 Dafidi si bẹ̀ Ọlọrun nitori ọmọ na, Dafidi si gbàwẹ, o si wọ inu ile lọ, o si dubulẹ lori ilẹ li oru na. 17 Awọn agbà ile rẹ̀ si dide tọ̀ ọ lọ, lati gbe e dide lori ilẹ: o si kọ̀, kò si ba wọn jẹun. 18 O si ṣe, ni ijọ keje, ọmọ na si kú. Awọn iranṣẹ Dafidi si bẹ̀ru lati wi fun u pe, ọmọ na kú: nitori ti nwọn wipe, Kiye si i, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, awa sọ̀rọ fun u, on kò si gbọ́ ohùn wa: njẹ yio ti ṣẹ́ ara rẹ̀ ni iṣẹ́ to, bi awa ba wi fun u pe, ọmọ na kú? 19 Nigbati Dafidi si ri pe awọn iranṣẹ rẹ̀ nsọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ, Dafidi si kiye si i pe ọmọ na kú: Dafidi si bere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ọmọ na kú bi? nwọn si da a li ohùn pe, O kú. 20 Dafidi si dide ni ilẹ, o si wẹ̀, o fi ororo pa ara, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si wọ inu ile Oluwa lọ, o si wolẹ sìn: o si wá si ile rẹ̀ o si bere, nwọn si gbe onjẹ kalẹ niwaju rẹ̀, o si jẹun. 21 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si bi li ere pe, Ki li eyi ti iwọ ṣe yi? nitori ọmọ na nigbati o mbẹ lãye iwọ gbawẹ, o si sọkun; ṣugbọn nigbati ọmọ na kú, o dide o si jẹun. 22 O si wipe, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, emi gbawẹ, emi si sọkun: nitoriti emi wipe, Tali o mọ̀ bi Ọlọrun o ṣãnu mi, ki ọmọ na ki o le yè. 23 Ṣugbọn nisisiyi o ti kú, nitori kili emi o ṣe ma gbawẹ? emi le mu u pada wá mọ bi? emi ni yio tọ̀ ọ lọ, on ki yio si tun tọ̀ mi wá.

Wọ́n Bí Solomoni

24 Dafidi si ṣipẹ fun Batṣeba aya rẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ, o si ba a dapọ̀: on si bi ọmọkunrin kan, Dafidi si sọ orukọ rẹ̀ ni Solomoni: Oluwa si fẹ ẹ. 25 O si rán Natani woli, o si pe orukọ rẹ̀ ni Jedidiah nitori ti Oluwa.

Dafidi Ṣẹgun Raba

26 Joabu si ba Rabba ti awọn ọmọ Ammoni jagun, o si gbà ilu ọba wọn. 27 Joabu si ran awọn iranṣẹ si Dafidi, o si wipe, emi ti ba Rabba jà, emi si ti gbà ilu olomi wọnni. 28 Njẹ nitorina kó awọn enia iyokù jọ, ki o si do ti ilu na, ki o si gbà a, ki emi ki o má ba gbà ilu na, ki a ma ba pè e li orukọ mi. 29 Dafidi si kó gbogbo enia na jọ, o si lọ si Rabba, o si ba a jà, o si gbà a. 30 On si gba adé ọba wọn kuro li ori rẹ̀, wuwo rẹ̀ si jẹ talenti wura kan, o si ni okuta oniyebiye lara rẹ̀: a si fi i de Dafidi li ori. On si kó ikogun ilu na li ọ̀pọlọpọ. 31 On si kó awọn enia na ti o wà ninu rẹ̀, o si fi wọn si iṣẹ ayùn, ati si iṣẹ nkan iwọlẹ ti a fi irin ṣe, ati si iṣẹ ãke irin, o si fi wọn si iṣẹ biriki mímọ: bẹ̃na li on si ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Dafidi ati gbogbo awọn enia na si pada si Jerusalemu.

2 Samueli 13

Amnoni ati Tamari

1 O si ṣe, lẹhin eyi, Absalomu ọmọ Dafidi ni aburo obinrin kan ti o ṣe arẹwà, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi si fẹràn rẹ̀. 2 Amnoni si banujẹ titi o fi ṣe aisan nitori Tamari aburo rẹ̀ obinrin; nitoripe wundia ni; o si ṣe ohun ti o ṣoro li oju Amnoni lati ba a ṣe nkan kan. 3 Ṣugbọn Amnoni ni ọrẹ́ kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹgbọ́n Dafidi: Jonadabu si jẹ alarekereke enia gidigidi. 4 O si wi fun u pe, ẽṣe ti iwọ ọmọ ọba nfi nrù lojojumọ bayi? o kì yio ha sọ fun mi? Amnoni si wi fun u pe, emi fẹ Tamari aburo Absalomu arakunrin mi. 5 Jonadabu si wi fun u pe, dubulẹ ni ibusùn rẹ ki iwọ ki o si ṣe bi ẹnipe ara rẹ kò yá: baba rẹ yio si wá iwò ọ, iwọ o si wi fun u pe, Jọ̀wọ jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá ki o si fun mi li onjẹ ki o si se onjẹ na niwaju mi ki emi ki o ri i, emi o si jẹ ẹ li ọwọ́ rẹ̀. 6 Amnoni si dubulẹ, o si ṣe bi ẹnipe on ṣaisan: ọba si wá iwò o, Amnoni si wi fun ọba pe, Jọwọ, jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá, ki o si din akarà meji li oju mi, emi o si jẹ li ọwọ́ rẹ̀. 7 Dafidi si ranṣẹ si Tamari ni ile pe, Lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ, ki o si ṣe ti onjẹ fun u. 8 Tamari si lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀, on si mbẹ ni ibulẹ. Tamari si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara li oju rẹ̀, o si din akara na. 9 On si mu awo na, o si dà a sinu awo miran niwaju rẹ̀; ṣugbọn o kọ̀ lati jẹ. Amnoni si wipe, jẹ ki gbogbo ọkunrin jade kuro lọdọ mi. Nwọn si jade olukuluku ọkunrin kuro lọdọ rẹ̀. 10 Amnoni si wi fun Tamari pe, mu onjẹ na wá si yara, emi o si jẹ lọwọ rẹ. Tamari si mu akara ti o ṣe, o si mu u tọ̀ Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀ ni iyẹwu. 11 Nigbati o si sunmọ ọ lati fi onjẹ fun u, on si di i mu, o si wi fun u pe, wá dubulẹ tì mi, aburo mi. 12 On si da a lohùn wipe, Bẹ̃kọ ẹgbọ́n mi, máṣe tẹ́ mi; nitoripe ko tọ́ ki a ṣe iru nkan bẹ̃ ni Israeli, iwọ máṣe huwa were yi. 13 Ati emi, nibo li emi o gbe itiju mi wọ̀? iwọ o si dabi ọkan ninu awọn aṣiwere ni Israeli. Njẹ nitorina, emi bẹ̀ ọ, sọ fun ọba; nitoripe on kì yio kọ̀ lati fi mi fun ọ. 14 Ṣugbọn o kọ̀ lati gbọ́ ohùn rẹ̀; o si fi agbara mu u, o si ṣẹgun rẹ̀, o si ba a dapọ̀. 15 Amnoni si korira rẹ̀ gidigidi, irira na si wá jù ifẹ ti on ti ni si i ri lọ. Amnoni si wi fun u pe, Dide, ki o si ma lọ. 16 On si wi fun u pe, Ko ha ni idi bi; lilé ti iwọ nlé mi yi buru jù eyi ti iwọ ti ṣe si mi lọ. Ṣugbọn on ko fẹ gbọ́ tirẹ̀. 17 On si pe ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti iṣe iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun u pe, Jọwọ, tì obinrin yi sode fun mi, ki o si ti ilẹkùn mọ ọ. 18 On si ni aṣọ alaràbara kan li ara rẹ̀: nitori iru aṣọ awọ̀leke bẹ̃ li awọn ọmọbinrin ọba ti iṣe wundia ima wọ̀. Iranṣẹ rẹ̀ si mu u jade, o si ti ilẹkun mọ ọ. 19 Tamari si bu ẽru si ori rẹ̀, o si fa aṣọ alaràbara ti mbẹ lara rẹ̀ ya, o si ka ọwọ́ rẹ̀ le ori, o si nkigbe bi o ti nlọ. 20 Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀ si bi i lere pe, Amnoni ẹgbọ́n rẹ ba ọ ṣe bi? njẹ aburo mi, dakẹ; ẹgbọ́n rẹ ni iṣe; má fi nkan yi si ọkàn rẹ. Tamari si joko ni ibanujẹ ni ile Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀. 21 Ṣugbọn nigbati Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi. 22 Absalomu ko si ba Amnoni sọ nkan, rere, tabi buburu: nitoripe Absalomu korira Amnoni nitori eyi ti o ṣe, ani ti o fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀.

Absalomu Gbẹ̀san

23 O si ṣe, lẹhin ọdun meji, Absalomu si ni olurẹrun agutan ni Baal-hasori, eyiti o gbè Efraimu: Absalomu si pe gbogbo awọn ọmọ ọba. 24 Absalomu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Wõ, jọwọ, iranṣẹ rẹ ni olurẹrun agutan, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ ba iranṣẹ rẹ lọ. 25 Ọba si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, má jẹ ki gbogbo wa lọ, ki a má mu ọ nawo pupọ. O si rọ̀ ọ gidigidi, ṣugbọn on kò fẹ lọ, o si sure fun u. 26 Absalomu si wi pe, Bi kò ba le ri bẹ̃, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Amnoni ẹgbọ́n mi ba wa lọ. Ọba si wipe, Idi rẹ̀ ti yio fi ba ọ lọ? 27 Absalomu si rọ̀ ọ, on si jẹ ki Amnoni ati gbogbo awọn ọmọ ọba ba a lọ. 28 Absalomu si fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ki ẹnyin ki o ma kiyesi akoko ti ọti-waini yio mu ọkàn Amnoni dùn, emi o si wi fun nyin pe, Kọlu Amnoni; ki ẹ si pa a: ẹ má bẹ̀ru: ṣe emi li o fi aṣẹ fun nyin? ẹ ṣe giri, ki ẹ ṣe bi alagbara ọmọ. 29 Awọn iranṣẹ Absalomu si ṣe si Amnoni gẹgẹ bi Absalomu ti paṣẹ. Gbogbo awọn ọmọ ọba si dide, olukuluku gun ibaka rẹ̀, nwọn si sa. 30 O si ṣe, nigbati nwọn mbẹ li ọ̀na, ihìn si de ọdọ Dafidi pe, Absalomu pa gbogbo awọn ọmọ ọba, ọkan kò si kù ninu wọn. 31 Ọba si dide, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si dubulẹ ni ilẹ; gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti nwọn duro tì i si fa aṣọ wọn ya. 32 Jonadabu ọmọ Ṣimea arakonrin Dafidi si dahùn o si wipe, Ki oluwa mi ọba ki o máṣe rò pe nwọn ti pa gbogbo awọn ọdọmọde-kọnrin awọn ọmọ ọba; nitoripe Amnoni nikanṣoṣo li o kú: nitori lati ẹnu Absalomu wá li a ti pinnu rẹ̀ lati ọjọ ti o ti fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀. 33 Njẹ ki oluwa mi ọba ki o máṣe fi nkan yi si ọkàn pe, gbogbo awọn ọmọ ọba li o kú: nitori Amnoni nikanṣoṣo li o kú. 34 Absalomu si sa. Ọdọmọkunrin na ti nṣọ̀na si gbe oju rẹ̀ soke, o si ri pe, ọ̀pọ enia mbọ̀ li ọ̀na lẹhin rẹ̀ lati iha oko wá. 35 Jonadabu si wi fun ọba pe, Wõ, awọn ọmọ ọba mbọ̀: gẹgẹ bi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ, bẹ̃ li o ri. 36 O si ṣe, nigbati o ti pari ọ̀rọ isọ, si wõ, awọn ọmọ ọba de, nwọn si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun: ọba ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu si sọkun nlanla. 37 Absalomu si sa, o si tọ̀ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi si nkãnu nitori ọmọ rẹ̀ lojojumọ. 38 Absalomu si sa, o si lọ si Geṣuri, o si gbe ibẹ li ọdun mẹta. 39 Ọkàn Dafidi ọba si fà gidigidi si Absalomu: nitoriti o ti gbà ipẹ̀ niti Amnoni: o sa ti kú.

2 Samueli 14

Joabu ṣe ètò àtipadà Absalomu

1 JOABU ọmọ Seruia si kiyesi i pe, ọkàn ọba si fà si Absalomu. 2 Joabu si ranṣẹ si Tekoa, o si mu ọlọgbọn obinrin kan lati ibẹ̀ wá, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, ṣe bi ẹniti nṣọfọ, ki o si fi aṣọ ọfọ sara, ki o má si ṣe fi ororo pa ara, ki o si dabi obinrin ti o ti nṣọ̀fọ fun okú li ọjọ pupọ̀. 3 Ki o si tọ̀ ọba wá, ki o si sọ fun u gẹgẹ bi ọ̀rọ yi. Joabu si fi ọ̀rọ si i li ẹnu. 4 Nigbati obinrin ará Tekoa na si nfẹ sọ̀rọ fun ọba, o wolẹ, o dojubolẹ, o si bu ọla fun u, o si wipe, Ọba, gbà mi. 5 Ọba si bi i lere pe, Ki li o ṣe ọ? on si dahùn wipe, Nitõtọ, opó li emi iṣe, ọkọ mi si kú. 6 Iranṣẹbinrin rẹ si ti li ọmọkunrin meji, awọn mejeji si jọ jà li oko, kò si si ẹniti yio là wọn, ekini si lu ekeji, o si pa a. 7 Si wõ, gbogbo idile dide si iranṣẹbinrin rẹ, nwọn si wipe, Fi ẹni ti o pa ẹnikeji rẹ̀ fun wa, awa o si pa a ni ipo ẹmi ẹnikeji rẹ̀ ti o pa, awa o si pa arole na run pẹlu: nwọn o si pa iná mi ti o kù, nwọn kì yio si fi orukọ tabi ẹni ti o kù silẹ fun ọkọ mi li aiye. 8 Ọba si wi fun obinrin na pe, Lọ si ile rẹ. emi o si kilọ nitori rẹ. 9 Obinrin ara Tekoa na si wi fun ọba pe, Oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀ṣẹ na ki o wà lori mi, ati lori idile baba mi; ki ọba ati itẹ rẹ̀ ki o jẹ́ alailẹbi. 10 Ọba si wipe, Ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ si ọ, mu oluwa rẹ̀ tọ̀ mi wá, on kì yio si tọ́ ọ mọ. 11 O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ, 12 Obinrin na si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o sọ̀rọ kan fun oluwa mi ọba; on si wipe, Ma wi. 13 Obinrin na si wipe, Nitori kini iwọ si ṣe ro iru nkan yi si awọn enia Ọlọrun? nitoripe ọba si sọ nkan yi bi ẹniti o jẹbi, nitipe ọba kò mu isánsa rẹ̀ bọ̀ wá ile. 14 Nitoripe awa o sa kú, a o si dabi omi ti a tú silẹ ti a kò si le ṣajọ mọ; nitori bi Ọlọrun kò ti gbà ẹmi rẹ̀, o si ti ṣe ọna ki a má bà lé isánsa rẹ̀ kuro lọdọ rẹ̀. 15 Njẹ nitorina li emi si ṣe wá isọ nkan yi fun oluwa mi ọba, bi o jẹpe awọn enia ti dẹrubà mi; iranṣẹbinrin rẹ si wi pe, Njẹ emi o sọ fun ọba; o le ri bẹ̃ pe ọba yio ṣe ifẹ iranṣẹbinrin rẹ̀ fun u. 16 Nitoripe ọba o gbọ́, lati gbà iranṣẹbinrin rẹ̀ silẹ lọwọ ọkunrin na ti o nfẹ ke emi ati ọmọ mi pẹlu kuro ninu ilẹ ini Ọlọrun. 17 Iranṣẹbinrin rẹ si wipe, Njẹ ọ̀rọ ọba oluwa mi yio si jasi itùnu: nitori bi angeli Ọlọrun bẹ̃ ni oluwa mi ọba lati mọ̀ rere ati buburu: Oluwa Ọlọrun rẹ yio si wà pẹlu rẹ. 18 Ọba si dahùn, o si wi fun obinrin na pe, Máṣe fi nkan ti emi o bere lọwọ rẹ pamọ fun mi, emi bẹ̀ ọ. Obinrin na si wipe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mã wi. 19 Ọba si wipe, Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹlu rẹ ninu gbogbo eyi? obinrin na si dahun o si wipe, Bi ẹmi rẹ ti mbẹ lãye, oluwa mi ọba, kò si iyipada si ọwọ́ ọtun, tabi si ọwọ́ osi ninu gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti wi: nitoripe Joabu iranṣẹ rẹ, on li o rán mi, on li o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi si iranṣẹbinrin rẹ li ẹnu. 20 Lati mu iru ọ̀rọ wọnyi wá ni Joabu iranṣẹ rẹ si ṣe nkan yi: oluwa mi si gbọ́n, gẹgẹ bi ọgbọ́n angeli Ọlọrun, lati mọ̀ gbogbo nkan ti mbẹ li aiye. 21 Ọba si wi fun Joabu pe, Wõ, emi o ṣe nkan yi: nitorina lọ, ki o si mu ọmọdekunrin na Absalomu pada wá. 22 Joabu si wolẹ o doju rẹ̀ bolẹ, o si tẹriba fun u, o si sure fun ọba: Joabu si wipe, Loni ni iranṣẹ rẹ mọ̀ pe, emi ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, oluwa mi, ọba, nitoripe ọba ṣe ifẹ iranṣẹ rẹ. 23 Joabu si dide, o si lọ si Geṣuri, o si mu Absalomu wá si Jerusalemu. 24 Ọba si wipe, Jẹ ki o yipada lọ si ile rẹ̀, má si ṣe jẹ ki o ri oju mi. Absalomu si yipada si ile rẹ̀, kò si ri oju ọba. 25 Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rẹ̀ titi de atari rẹ̀ kò si abùkun kan lara rẹ̀.

Ìjà Parí láàrin Absalomu ati Dafidi

26 Nigbati o ba si rẹ́ irun ori rẹ̀ (nitoripe li ọdọdun li on ima rẹ́ ẹ nitoriti o wuwo fun u, on a si ma rẹ́ ẹ) on si wọ̀n irun ori rẹ̀, o si jasi igba ṣekeli ninu òṣuwọn ọba. 27 A si bi ọmọkunrin mẹta fun Absalomu ati ọmọbinrin kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari: on si jẹ obinrin ti o li ẹwà loju. 28 Absalomu si joko li ọdun meji ni Jerusalemu kò si ri oju ọba. 29 Absalomu si ranṣẹ si Joabu, lati rán a si ọba; ṣugbọn on kò fẹ wá sọdọ rẹ̀; o si ranṣẹ lẹ̃keji on kò si fẹ wá. 30 O si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, oko Joabu gbè ti emi, o si ni ọkà nibẹ; ẹ lọ ki ẹ si tinabọ̀ ọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si tinabọ oko na. 31 Joabu si dide, o si tọ Absalomu wá ni ile, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti awọn iranṣẹ rẹ fi tinabọ oko mi? 32 Absalomu si da Joabu lohùn pe, Wõ, emi ranṣẹ si ọ, wipe, Wá nihinyi, emi o si rán ọ lọ sọdọ ọba, lati wi pe, Kili emi ti Geṣuri wá si? iba sàn fun mi bi o ṣepe emi wà nibẹ̀ sibẹ. Njẹ emi nfẹ ri oju ọba; bi o ba si ṣe pe ẹ̀ṣẹ mbẹ li ara mi, ki o pa mi. 33 Joabu si tọ̀ ọba wá, o si rò fun u: o si ranṣẹ pe Absalomu, on si wá sọdọ ọba, o tẹriba fun u, o si doju rẹ̀ bolẹ niwaju ọba; ọba si fi ẹnu ko Absalomu li ẹnu.

2 Samueli 15

Absalomu dìtẹ̀ mọ́ Dafidi

1 O si ṣe lẹhin eyi, Absalomu si pèse kẹkẹ́ ati ẹṣin fun ara rẹ̀, ati adọta ọmọkunrin ti yio ma sare niwaju rẹ̀. 2 Absalomu si dide ni kutukutu, o si duro li apakan ọ̀na ẹnu ibode: o si ṣe, bi ẹnikan ba ni ẹjọ ti o nfẹ mu tọ̀ ọba wá fun idajọ, a si pè e sọdọ rẹ̀, a si bi i pe, Ara ilu wo ni iwọ? on a si dahùn pe, Iranṣẹ rẹ ti inu ọkan ninu ẹya Israeli wá. 3 Absalomu a si wi fun u pe Wõ, ọ̀ran rẹ sa dara, o si tọ: ṣugbọn ko si ẹnikan ti ọba fi aṣẹ fun lati yẹ ọ̀ran rẹ wò. 4 Absalomu a si wipe, A ba jẹ fi mi ṣe onidajọ ni ilẹ yi! ki olukuluku ẹniti o ni ẹjọ tabi ọ̀ran kan ba le ma tọ̀ mi wa, emi iba si ṣe idajọ otitọ fun u. 5 Bẹ̃ni bi ẹnikan ba si sunmọ ọ lati tẹriba fun u, on a si nawọ́ rẹ̀, a si dì i mu, a si fi ẹnu kò o li ẹnu. 6 Iru iwà bayi ni Absalomu a ma hù si gbogbo Israeli ti o tọ̀ ọba wá nitori idajọ: Absalomu si fa ọkàn awọn enia Israeli sọdọ rẹ̀. 7 O si ṣe lẹhin ogoji ọdun, Absalomu si wi fun ọba pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o lọ, ki emi o si san ileri mi ti emi ti ṣe fun Oluwa, ni Hebroni. 8 Nitori ti iranṣẹ rẹ ti jẹ'jẹ kan nigbati emi mbẹ ni Geṣuri ni Siria, pe, Bi Oluwa ba mu mi pada wá si Jerusalemu, nitotọ, emi o si sin Oluwa. 9 Ọba si wi fun u pe, Ma lọ li alafia. O si dide, o si lọ si Hebroni. 10 Ṣugbọn Absalomu rán amí sarin gbogbo ẹyà Israeli pe, Nigbati ẹnyin ba gbọ́ iró ipè, ki ẹnyin si wipe, Absalomu jọba ni Hebroni. 11 Igba ọkunrin si bá Absalomu ti Jerusalemu jade, ninu awọn ti a ti pè; nwọn si lọ ninu aimọ̀kan wọn, nwọn kò si mọ nkankan. 12 Absalomu si ranṣẹ pè Ahitofeli ara Giloni, igbimọ̀ Dafidi, lati ilu rẹ̀ wá, ani lati Gilo, nigbati o nrú ẹbọ. Idìtẹ̀ na si le; awọn enia si npọ̀ sọdọ Absalomu.

Dafidi Sá Kúrò ní Jerusalẹmu

13 Ẹnikan si wá rò fun Dafidi pe, Ọkàn awọn ọkunrin Israeli ṣi si Absalomu. 14 Dafidi si wi fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ ni Jerusalemu pe, Ẹ dide, ẹ jẹ ki a salọ, nitoripe kò si ẹniti yio gbà wa lọwọ Absalomu: ẹ yara, ki a lọ kuro, ki on má ba yara le wa ba, ki o má si mu ibi ba wa, ki o má si fi oju idà pa ilu run. 15 Awọn iranṣẹ ọba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa wa ọba nfẹ, wõ, awa iranṣẹ rẹ ti mura. 16 Ọba si jade, gbogbo ile rẹ̀ si tẹle e. Ọba si fi mẹwa ninu awọn obinrin rẹ̀ silẹ lati ma ṣọ ile. 17 Ọba si jade, gbogbo enia si tẹle e, nwọn si duro ni ibikan ti o jina. 18 Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ si kọja li ọtún li osì rẹ̀, ati gbogbo awọn Kereti, ati gbogbo awọn Peleti, ati gbogbo awọn Giti, ẹgbẹta ọmọkunrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Gati wá, si kọja niwaju ọba. 19 Ọba si wi fun Ittai, ara Giti nì pe, Ẽṣe ti iwọ fi mba wa lọ pẹlu? pada, ki o si ba ọba joko: nitoripe alejo ni iwọ, iwọ si ti fi ilu rẹ silẹ. 20 Lana yi ni iwọ de, emi ha si le mu ki iwọ ma ba wa lọ kakiri loni bi? emi nlọ si ibikibi ti mo ba ri: pada, ki o si mu awọn arakunrin rẹ pada, ki ãnu ati otitọ ki o pẹlu rẹ. 21 Ittai si da ọba lohùn, o si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ati bi oluwa mi ọba ti mbẹ lãye, nitotọ nibikibi ti oluwa mi ọba ba gbe wà, ibakàn ṣe ninu ikú, tabi ninu ìye, nibẹ pẹlu ni iranṣẹ rẹ yio gbe wà. 22 Dafidi si wi fun Ittai pe, Lọ ki o si rekọja. Ittai ará Giti nì si rekọja, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ kekeke ti o wà lọdọ rẹ̀. 23 Gbogbo ilu na si fi ohùn rara sọkun, gbogbo enia si rekọja; ọba si rekọja odo Kidroni, gbogbo awọn enia na si rekọja, si ihà ọ̀na iju. 24 Si wõ, Sadoku pẹlu ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o wà lọdọ rẹ̀ si nru apoti-ẹri Ọlọrun: nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na kalẹ; Abiatari si goke, titi gbogbo awọn enia si fi dẹkun ati ma kọja lati ilu wá. 25 Ọba si wi fun Sadoku pe, Si tun gbe apoti-ẹri Ọlọrun na pada si ilu: bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ Oluwa, yio si tun mu mi pada wá, yio si fi apoti-ẹri na hàn mi ati ibugbe rẹ̀. 26 Ṣugbọn bi on ba si wi pe, Emi kò ni inu didùn si ọ; wõ, emi niyi, jẹ ki on ki o ṣe si mi gẹgẹ bi o ti tọ́ li oju rẹ̀. 27 Ọba si wi fun Sadoku alufa pe, Iwọ kọ́ ariran? pada si ilu li alafia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ, Ahimaasi ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari. 28 Wõ, emi o duro ni pẹtẹlẹ iju nì, titi ọ̀rọ o fi ti ọdọ rẹ wá lati sọ fun mi. 29 Sadoku ati Abiatari si gbe apoti-ẹri Ọlọrun pada si Jerusalemu: nwọn si gbe ibẹ̀. 30 Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rẹ̀, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀, olukuluku ọkunrin si bò ori rẹ̀, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ. 31 Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan. 32 O si ṣe, Dafidi de ori oke, nibiti o gbe wolẹ̀ sin Ọlọrun, si wõ, Huṣai ara Arki nì si wá lati pade rẹ̀ ti on ti aṣọ rẹ̀ yiya, ati erupẹ, li ori rẹ̀. 33 Dafidi si wi fun u pe, bi iwọ ba bá mi kọja, iwọ o si jẹ idiwọ fun mi. 34 Bi iwọ ba si pada si ilu, ti o si wi fun Absalomu pe, Emi o ṣe iranṣẹ rẹ, ọba, gẹgẹ bi emi ti ṣe iranṣẹ baba rẹ nigba atijọ, bẹ̃li emi o si jẹ iranṣẹ rẹ nisisiyi: ki iwọ ki o si bà ìmọ Ahitofeli jẹ. 35 Ṣe Sadoku ati Abiatari awọn alufa wà nibẹ pẹlu rẹ? yio si ṣe, ohunkohun ti iwọ ba gbọ́ lati ile ọba wá, iwọ o si sọ fun Sadoku ati Abiatari awọn alufa. 36 Wõ, nwọn si ni ọmọ wọn mejeji nibẹ pẹlu wọn, Ahimaasi ọmọ Sadoku, ati Jonatani ọmọ Abiatari; lati ọwọ́ wọn li ẹnyin o si rán ohunkohun ti ẹnyin ba gbọ́ si mi. 37 Huṣai ọrẹ Dafidi si wá si ilu, Absalomu si wá si Jerusalemu.

2 Samueli 16

Dafidi ati Siba

1 NIGBATI Dafidi si fi diẹ kọja ori oke na, si wõ, Siba iranṣẹ Mefiboṣeti si mbọ̀ wá ipade rẹ̀, ti on ti kẹtẹkẹtẹ́ meji ti a ti dì li asá, ati igba iṣu akara li ori wọn, ati ọgọrun ṣiri ajara gbigbẹ, ati ọgọrun eso ẹrùn, ati igò ọti-waini kan. 2 Ọba si wi fun Siba pe, Kini wọnyi? Siba si wipe, Kẹtẹkẹtẹ wọnyi ni fun awọn ara ile ọba lati ma gùn; ati akara yi, ati eso ẹrùn yi ni fun awọn ọdọmọdekunrin lati jẹ; ati ọti-waini yi ni fun awọn alãrẹ ni ijù lati mu. 3 Ọba si wipe, Ọmọ oluwa rẹ da? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, o joko ni Jerusalemu; nitoriti o wipe, Loni ni idile Israeli yio mu ijọba baba mi pada fun mi wá. 4 Ọba si wi fun Siba pe, Wõ, gbogbo nkan ti iṣe ti Mefiboṣeti jẹ tirẹ. Siba si wipe, Mo tũba, jẹki nri ore-ọfẹ loju rẹ, oluwa mi, Ọba.

Dafidi ati Ṣimei

5 Dafidi ọba si de Bahurimu, si wõ, ọkunrin kan ti ibẹ̀ jade wá, lati idile Saulu wá, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ṣimei, ọmọ Gera: o si nyan ẹ̃bu bi o ti mbọ̀. 6 O si sọ okuta si Dafidi, ati si gbogbo iranṣẹ Dafidi ọba, ati si gbogbo awọn enia, gbogbo awọn alagbara ọkunrin si wà lọwọ ọtún rẹ̀ ati lọwọ osì rẹ̀. 7 Bayi ni Ṣimei si wi nigbati o nyan ẽbu, Jade, jade, iwọ ọkunrin ẹjẹ, iwọ ọkunrin Beliali. 8 Oluwa mu gbogbo ẹjẹ idile Saulu pada wá si ori rẹ, ni ipo ẹniti iwọ jọba; Oluwa ti fi ijọba na le Absalomu ọmọ rẹ lọwọ: si wõ, ìwa buburu rẹ li o mu eyi wá ba ọ, nitoripe ọkunrin ẹjẹ ni iwọ. 9 Abiṣai ọmọ Seruia si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti okú ajá yi fi mbu oluwa mi ọba? jẹ ki emi kọja, emi bẹ̀ ọ, ki emi si bẹ́ ẹ li ori. 10 Ọba si wipe, Kili emi ni fi nyin ṣe, ẹnyin ọmọ Seruia? jẹ ki o ma bu bẹ̃, nitoriti Oluwa ti wi fun u pe: Bu Dafidi. Tani yio si wipe, Nitori kini iwọ fi ṣe bẹ̃? 11 Dafidi si wi fun Abiṣai, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rẹ̀, si jẹ ki o ma yan ẽbu; nitoripe Oluwa li o fi rán an. 12 Bọ́ya Oluwa yio wo ipọnju mi, Oluwa yio si fi ire san a fun mi ni ipo ẽbu rẹ̀ loni. 13 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nlọ li ọ̀na, Ṣimei si nrìn li ẹba oke ti o wà li ẹgbẹ rẹ̀, o si nyan ẽbu bi o ti nlọ, o si nsọ ọ li okuta, o si nfún erupẹ. 14 Ọba, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si wá ti awọn ti ãrẹ̀, nwọn si simi nibẹ. 15 Absalomu ati gbogbo awọn enia, awọn ọkunrin Israeli si wá si Jerusalemu, Ahitofeli si wà pẹlu rẹ̀.

Absalomu ní Jerusalẹmu

16 O si ṣe, nigbati Huṣai ará Arki, ọrẹ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai si wi fun Absalomu pe, Ki ọba ki o pẹ, ki ọba ki o pẹ. 17 Absalomu si wi fun Huṣai pe, Ore rẹ si ọ̀rẹ rẹ ni eyi? ẽṣe ti iwọ kò ba ọrẹ rẹ lọ? 18 Huṣai si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ nitori ẹniti Oluwa, ati gbogbo awọn enia yi, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ba yàn, tirẹ̀ li emi o jẹ, on li emi o si ba joko. 19 Ẹwẹ̀, tani emi o si sìn? kò ha yẹ ki emi ki o ma sìn niwaju ọmọ rẹ̀? gẹgẹ bi emi ti nsìn ri niwaju baba rẹ, bẹ̃li emi o ri niwaju rẹ. 20 Absalomu si wi fun Ahitofeli pe, Ẹ ba ara nyin gbìmọ ohun ti awa o ṣe. 21 Ahitofeli si wi fun Absalomu pe, Wọle tọ awọn obinrin baba rẹ lọ, awọn ti o fi silẹ lati ma ṣọ ile, gbogbo Israeli yio si gbọ́ pe, iwọ di ẹni-irira si baba rẹ, ọwọ́ gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ yio si le. 22 Nwọn si tẹ agọ kan fun Absalomu li orile; Absalomu si wọle tọ awọn obinrin baba rẹ̀ li oju gbogbo Israeli. 23 Imọ̀ Ahitofeli ti ima gbà nijọ wọnni, o dabi ẹnipe enia mbere nkan li ọwọ́ Ọlọrun: bẹ̃ni gbogbo ìmọ Ahitofeli fun Dafidi ati fun Absalomu si ri.

2 Samueli 17

Huṣai Ṣi Absalomu lọ́nà

1 AHITOFELI si wi fun Absalomu pe, Emi o si yan ẹgbãfa ọkunrin emi o si dide, emi o si lepa Dafidi li oru yi. 2 Emi o si yọ si i nigbati ãrẹ̀ ba mu u ti ọwọ́ rẹ̀ si ṣe alaile, emi o si dá ipaiya bá a; gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ yio si sa, emi o si kọlu ọba nikanṣoṣo: 3 Emi o si mu gbogbo awọn enia pada sọdọ rẹ; ọkunrin na ti iwọ nwá si ri gẹgẹ bi ẹnipe gbogbo wọn ti pada: gbogbo awọn enia yio si wà li alafia. 4 Ọrọ na si tọ loju Absalomu, ati li oju gbogbo awọn agbà Israeli. 5 Absalomu si wipe, Njẹ̀ pe Huṣai ará Arki, awa o si gbọ́ eyi ti o wà li ẹnu rẹ̀ pẹlu. 6 Huṣai si de ọdọ Absalomu, Absalomu si wi fun u pe, Bayi ni Ahitofeli wi, ki awa ki o ṣe bi ọ̀rọ rẹ̀ bi? bi kò ba si tọ bẹ̃, iwọ wi. 7 Huṣai si wi fun Absalomu pe, Imọ̀ ti Ahitofeli gbà nì, ko dara nisisiyi. 8 Huṣai si wipe, Iwọ mọ̀ baba rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe alagbara ni nwọn, nwọn si wà ni kikoro ọkàn bi amọ̀tẹkun ti a gbà li ọmọ ni igbẹ: baba rẹ si jẹ jagunjagun ọkunrin, kì yio ba awọn enia na gbe pọ̀ li oru. 9 Kiyesi i o ti fi ara rẹ̀ pamọ nisisiyi ni iho kan, tabi ni ibomiran: yio si ṣe, nigbati diẹ ninu wọn ba kọ ṣubu, ẹnikẹni ti o ba gbọ́ yio si wipe, Iparun si mbẹ ninu awọn enia ti ntọ̀ Absalomu lẹhin. 10 Ẹniti o si ṣe alagbara, ti ọkàn rẹ̀ si dabi ọkàn kiniun, yio si rẹ̀ ẹ: nitori gbogbo Israeli ti mọ̀ pe alagbara ni baba rẹ, ati pe, awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ jẹ alagbara. 11 Nitorina emi damọ̀ran pe, Ki gbogbo Israeli wọjọ pọ̀ sọ̀dọ rẹ, lati Dani titi dé Beerṣeba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọ̀pọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na. 12 Awa o si yọ si i nibikibi ti awa o gbe ri i, awa o si yi i ka bi irì iti sẹ̀ si ilẹ̀: ani ọkan kì yio kù pẹlu rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀. 13 Bi o ba si bọ si ilu kan, gbogbo Israeli yio si mu okùn wá si ilu na, awa o si fà a lọ si odo, titi a kì yio fi ri okuta kekeke kan nibẹ. 14 Absalomu ati gbogbo ọkunrin Israeli si wipe, Ìmọ Huṣai ara Arki sàn jù ìmọ Ahitofeli lọ. Nitori Oluwa fẹ lati yi ìmọ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa ki o le mu ibi wá sori Absalomu.

Dafidi sá fún ewu tí ń bọ̀

15 Huṣai si wi fun Sadoku ati fun Abiatari awọn alufa pe, Bayi bayi ni Ahitofeli ti ba Absalomu ati awọn agbà Israeli dámọran; bayi bayi li emi si damọràn. 16 Nitorina yara ranṣẹ nisisiyi ki o si sọ fun Dafidi pe, Máṣe duro ni pẹtẹlẹ ijù nì li alẹ yi, ṣugbọn yara rekọja, ki a má ba gbe ọba mì, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀. 17 Jonatani ati Ahimaasi si duro ni Enrogeli; ọdọmọdebirin kan si lọ, o si sọ fun wọn; awọn si lọ nwọn sọ fun Dafidi ọba nitoripe ki a má ba ri wọn pe nwọn wọ ilu. 18 Ṣugbọn ọdọmọdekunrin kan ri wọn, o si wi fun Absalomu: ṣugbọn awọn mejeji si yara lọ kuro, nwọn si wá si ile ọkunrin kan ni Bahurimu, ẹniti o ni kanga kan li ọgbà rẹ̀, nwọn si sọkalẹ si ibẹ. 19 Obinrin rẹ̀ si mu nkan o fi bo kanga na, o si sa agbado sori rẹ̀; a kò si mọ̀. 20 Awọn iranṣẹ Absalomu si tọ obinrin na wá ni ile na, nwọn si bere pe, Nibo ni Ahimaasi ati Jonatani gbe wà? obinrin na si wi fun wọn pe, Nwọn ti goke rekọja iṣan odo nì. Nwọn si wá wọn kiri, nwọn kò si ri wọn, nwọn si yipada si Jerusalemu. 21 O si ṣe, lẹhin igbati nwọn yẹra kuro tan, awọn si jade kuro ninu kanga, nwọn si lọ, nwọn si rò fun Dafidi ọba, nwọn si wi fun Dafidi pe, Dide ki o si goke odo kánkán: nitoripe bayi ni Ahitofeli gbìmọ si ọ. 22 Dafidi si dide, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si goke odo Jordani: ki ilẹ to mọ́, ẹnikan kò kù ti kò goke odo Jordani. 23 Nigbati Ahitofeli si ri pe nwọn kò fi ìmọ tirẹ̀ ṣe, o si di kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si dide, o lọ ile rẹ̀, o si palẹ ile rẹ̀ mọ, o si pokùnso, o si kú, a si sin i si iboji baba rẹ̀. 24 Dafidi si wá si Mahanaimu. Absalomu si goke odo Jordani, on, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli pẹlu rẹ̀. 25 Absalomu si fi Amasa ṣe olori ogun ni ipò Joabu: Amasa ẹniti iṣe ọmọ ẹnikan, orukọ ẹniti a npè ni Itra, ara Israeli, ti o wọle tọ Abigaili ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruia, iyá Joabu. 26 Israeli ati Absalomu si do ni ilẹ Gileadi. 27 O si ṣe, nigbati Dafidi si wá si Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba ti awọn ọmọ Ammoni, ati Makiri ọmọ Ammieli ti Lodebari, ati Barsillai ara Gileadi ti Rogelimu, 28 Mu akete, ati ago, ati ohun-elo amọ̀, ati alikama, ati ọkà, ati iyẹfun, ati agbado didin, ati ẹ̀wa, ati erẽ, ati ẹ̀wa didin. 29 Ati oyin, ati ori-amọ, ati agutan, ati wàrakasi malu, wá fun Dafidi, ati fun awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ lati jẹ: nitoriti nwọn wi pe, ebi npa awọn enia, o si rẹ̀ wọn, orungbẹ si ngbẹ wọn li aginju.

2 Samueli 18

Wọ́n ṣẹgun Absalomu, wọ́n sì Pa á

1 DAFIDI si kà awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, o si mu wọn jẹ balogun ẹgbẹgbẹrun, ati balogun ọrọrun lori wọn. 2 Dafidi si fi idamẹta awọn enia na le Joabu lọwọ, o si ran wọn lọ, ati idamẹta le Abiṣai ọmọ Seruia aburo Joabu lọwọ, ati idamẹta le Ittai ara Giti lọwọ. Ọba si wi fun awọn enia na pe, nitotọ emi tikara mi o si ba nyin lọ pẹlu. 3 Awọn enia na si wipe, Iwọ ki yio ba wa lọ: nitoripe bi awa ba sa, nwọn kì yio nani wa, tabi bi o tilẹ ṣepe idajì wa kú, nwọn ki yio nani wa, nitoripe iwọ nikan to ẹgbãrun wa: nitorina, o si dara ki iwọ ki o ma ràn wa lọwọ lati ilu wá. 4 Ọba si wi fun wọn pe, Eyi ti o ba tọ́ loju nyin li emi o ṣe. Ọba si duro li apakan ẹnu odi, gbogbo awọn enia na si jade ni ọ̀rọrún ati ni ẹgbẹgbẹrun. 5 Ọba si paṣẹ fun Joabu ati Abiṣai ati Ittai pe, Ẹ tọju ọdọmọkunrin na Absalomu fun mi. Gbogbo awọn enia na si gbọ́ nigbati ọba paṣẹ fun gbogbo awọn balogun nitori Absalomu. 6 Awọn enia na si jade lati pade Israeli ni pápá; ni igbó Efraimu ni nwọn gbe pade ijà na. 7 Nibẹ li a gbe pa awọn enia Israeli niwaju awọn iranṣẹ Dafidi, ọ̀pọlọpọ enia lo ṣubu li ọjọ na, ani ẹgbãwa enia. 8 Ogun na si fọ́n ka kiri lori gbogbo ilẹ na: igbógàn na si pa ọ̀pọ enia jù eyi ti idà pa lọ li ọjọ na. 9 Absalomu si pade awọn iranṣẹ Dafidi. Absalomu si gun ori ibaka kan, ibaka na si gba abẹ ẹka nla igi pọ́nhan kan ti o tobi lọ, ori rẹ̀ si kọ́ igi pọ́nhan na, on si rọ̀ soke li agbedemeji ọrun on ilẹ; ibaka na ti o wà labẹ rẹ̀ si lọ kuro. 10 Ọkunrin kan si ri i, o si wi fun Joabu pe, Wõ, emi ri Absalomu rọ̀ lãrin igi pọ́nhan kan. 11 Joabu si wi fun ọkunrin na ti o sọ fun u pe, Sa wõ, iwọ ri i, eha ti ṣe ti iwọ kò fi lù u bolẹ nibẹ? emi iba si fun ọ ni ṣekeli fadaka mẹwa, ati amure kan. 12 Ọkunrin na si wi fun Joabu pe, Biotilẹṣepe emi o gba ẹgbẹrun ṣekeli fadaka si ọwọ́ mi, emi kì yio fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nitoripe awa gbọ́ nigbati ọba kilọ fun iwọ ati Abiṣai, ati Ittai, pe, Ẹ kiye si i, ki ẹnikẹni ki o má fi ọwọ́ kan ọdọmọkunrin na Absalomu. 13 Bi o ba ṣe bẹ̃ emi iba ṣe ibi si ara mi: nitoripe kò si ọran kan ti o pamọ fun ọba, iwọ tikararẹ iba si kọju ijà si mi pẹlu. 14 Joabu si wipe, emi kì yio duro bẹ̃ niwaju rẹ. O si mu ọ̀kọ mẹta lọwọ rẹ̀, o si fi wọn gun Absalomu li ọkàn, nigbati o si wà lãye li agbedemeji igi pọ́nhan na. 15 Awọn ọdọmọdekunrin mẹwa ti ima ru ihamọra Joabu si yi Absalomu ka, nwọn si kọlù u, nwọn si pa a. 16 Joabu si fún ipè, awọn enia na si yipada ati mã lepa Israeli: nitori Joabu ti pe awọn enia na pada. 17 Nwọn si gbe Absalomu, nwọn si sọ ọ sinu iho nla kan ni igbogàn na, nwọn si papó okuta pupọ jọ si i lori, gbogbo Israeli si sa, olukuluku si inu agọ rẹ̀. 18 Absalomu li ọjọ aiye rẹ̀ si mu, o si mọ ọwọ̀n kan fun ara rẹ̀, ti mbẹ li afonifoji ọba: nitoriti o wipe, Emi kò ni ọmọkunrin ti yio pa orukọ mi mọ ni iranti: on si pe ọwọ̀n na nipa orukọ rẹ̀: a si npè e titi di oni, ni ọwọ̀n Absalomu.

Wọ́n túfọ̀ ikú Absalomu fún Dafidi

19 Ahimaasi ọmọ Sadoku si wipe, Jẹ ki emi ki o sure nisisiyi, ki emi ki o si mu ihìn tọ̀ ọba lọ, bi Oluwa ti gbẹsan rẹ̀ li ara awọn ọta rẹ̀. 20 Joabu si wi fun u pe, Iwọ ki yio mu ìhin lọ loni, ṣugbọn iwọ o mu ìhin lọ ni ijọ miran: ṣugbọn loni yi iwọ kì yio mu ìhin kan lọ, nitoriti ọmọ ọba ṣe alaisi. 21 Joabu si wi fun Kuṣi pe, Lọ, ki iwọ ki o rò ohun ti iwọ ri fun ọba. Kuṣi si wolẹ fun Joabu, o si sare. 22 Ahimaasi ọmọ Sadoku si tun wi fun Joabu pe, Jọwọ, bi o ti wu ki o ri, emi o sare tọ Kuṣi lẹhin. Joabu si bi i pe, Nitori kini iwọ o ṣe sare, ọmọ mi, iwọ kò ri pe kò si ihìn rere kan ti iwọ o mu lọ? 23 O si wi pe, Bi o ti wu ki o ri, emi o sare. On si wi fun u pe, Sare. Ahimaasi si sare li ọ̀na pẹtẹlẹ, o si sare kọja Kuṣi. 24 Dafidi si joko li ẹnu odi lãrin ilẹkun meji: alore si goke orule bode lori odi, o si gbe oju rẹ̀ soke, o si wò, wõ, ọkunrin kan nsare on nikan. 25 Alore na si kigbe, o si wi fun ọba; ọba si wi pe, Bi o ba ṣe on nikan ni, ihìn rere mbẹ li ẹnu rẹ̀. On si nsunmọ tosi. 26 Alore na si ri ọkunrin miran ti nsare: alore si kọ si ẹniti nṣọ bode, o si wi pe, Wõ, ọkunrin kan nsare on nikan, ọba si wipe, Eyi na pẹlu nmu ihìn rere wá. 27 Alore na si wipe, Emi wo isare ẹniti o wà niwaju o dabi isare Ahimaasi ọmọ Sadoku. Ọba si wi pe, Enia rere ni, o si nmu ihìn rere wá. 28 Ahimaasi si pè, o si wi fun ọba pe, Alafia. On si wolẹ fun ọba, o dojubolẹ o si wi pe, Alabukun fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ẹniti o fi awọn ọkunrin ti o gbe ọwọ́ wọn soke si oluwa mi ọba le ọ lọwọ. 29 Ọba si bere pe, Alafia fun Absalomu ọmọdekunrin nì bi? Ahimaasi si dahun pe, Nigbati Joabu rán iranṣẹ ọba, ati emi iranṣẹ rẹ, mo ri ọ̀pọ enia, ṣugbọn emi kò mọ̀ idi rẹ̀. 30 Ọba si wi fun u pe, Yipada ki o si duro nihin: On si yipada, o si duro jẹ. 31 Si wõ, Kuṣi de; Kuṣi si wi pe, Ihin rere fun oluwa mi ọba: nitoriti Oluwa ti gbẹsan rẹ loni lara gbogbo awọn ti o dide si ọ. 32 Ọba si bi Kuṣi pe, Alafia kọ Absalomu ọdọmọdekunrin na wà bi? Kuṣi si dahun pe, Ki awọn ọta oluwa mi ọba, ati gbogbo awọn ti o dide si ọ ni ibi, ri bi ọdọmọdekunrin na. 33 Ọba si kẹdùn pupọ̀, o si goke lọ si iyẹwu ti o wà lori oke bode, o si sọkun; bayi li o si nwi bi o ti nlọ, ọmọ mi Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi Absalomu! Ã! Ibaṣepe emi li o kú ni ipò rẹ, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!

2 Samueli 19

Joabu bínú sí Dafidi

1 A si rò fun Joabu pe, Wõ, ọba nsọkun, o si ngbawẹ fun Absalomu. 2 Iṣẹgun ijọ na si di awẹ̀ fun gbogbo awọn enia na, nitori awọn enia na gbọ́ ni ijọ na bi inu ọba ti bajẹ nitori ọmọ rẹ̀. 3 Awọn enia na si yọ́ lọ si ilu ni ijọ na gẹgẹ bi awọn enia ti a dojuti a ma yọ́ lọ nigbati nwọn nsá loju ijà. 4 Ọba si bo oju rẹ̀, ọba si kigbe li ohùn rara pe, A! ọmọ mi Absalomu, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi! 5 Joabu si wọ inu ile tọ ọba lọ, o si wipe, Iwọ dojuti gbogbo awọn iranṣẹ rẹ loni, awọn ti o gbà ẹmi rẹ là loni, ati ẹmi awọn ọmọkunrin rẹ, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ, ati ẹmi awọn aya rẹ, ati ẹmi awọn obinrin rẹ. 6 Nitoripe iwọ fẹ awọn ọta rẹ, iwọ si korira awọn ọrẹ rẹ. Nitoriti iwọ wi loni pe, Iwọ kò nani awọn ọmọ ọba, tabi awọn iranṣẹ: emi si ri loni pe, ibaṣepe Absalomu wà lãye, ki gbogbo wa si kú loni, njẹ iba dùnmọ ọ gidigidi. 7 Si dide nisisiyi, lọ, ki o si sọ̀rọ itùnú fun awọn iranṣẹ rẹ: nitoripe emi fi Oluwa bura, bi iwọ kò ba lọ, ẹnikan kì yio ba ọ duro li alẹ yi: ati eyini yio si buru fun ọ jù gbogbo ibi ti oju rẹ ti nri lati igbà ewe rẹ wá titi o fi di isisiyi. 8 Ọba si dide, o si joko li ẹnu ọ̀na. Nwọn si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Wõ, ọba joko li ẹnu ọ̀na. Gbogbo enia si wá si iwaju ọba: nitoripe, Israeli ti sa, olukuluku si àgọ́ rẹ̀.

Dafidi bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu

9 Gbogbo awọn enia na si mba ara wọn jà ninu gbogbo ẹya Israeli, pe, Ọba ti gbà wa là lọwọ awọn ọta wa, o si ti gbà wa kuro lọwọ awọn Filistini; on si wa sa kuro ni ilu nitori Absalomu. 10 Absalomu, ti awa fi jọba lori wa si kú li ogun: njẹ ẽṣe ti ẹnyin fi dakẹ ti ẹnyin kò si sọ̀rọ kan lati mu ọba pada wá? 11 Dafidi ọba si ranṣẹ si Sadoku, ati si Abiatari awọn alufa pe, Sọ fun awọn agbà Juda, pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá si ile rẹ̀? ọ̀rọ gbogbo Israeli si ti de ọdọ ọba ani ni ile rẹ̀. 12 Ẹnyin li ará mi, ẹnyin li egungun mi, ati ẹran ara mi: ẹ̃si ti ṣe ti ẹnyin fi kẹhìn lati mu ọba pada wá? 13 Ki ẹnyin ki o si wi fun Amasa pe, Egungun ati ẹran ara mi ki iwọ iṣe bi? ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si mi ati ju bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ kò ba ṣe olori ogun niwaju mi titi, ni ipò Joabu. 14 On si yi ọkàn gbogbo awọn ọkunrin Juda, ani bi ọkàn enia kan; nwọn si ranṣẹ si ọba, pe, Iwọ pada ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ. 15 Ọba si pada, o si wá si odo Jordani. Juda si wá si Gilgali, lati lọ ipade ọba, ati lati mu ọba kọja odo Jordani. 16 Ṣimei ọmọ Gera, ara Benjamini ti Bahurimu, o yara o si ba awọn ọkunrin Juda sọkalẹ lati pade Dafidi ọba. 17 Ẹgbẹrun ọmọkunrin si wà lọdọ rẹ̀ ninu awọn ọmọkunrin Benjamini, Siba iranṣẹ ile Saulu, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹ si pẹlu rẹ̀; nwọn si goke odo Jordani ṣaju ọba. 18 Ọkọ̀ èro kan ti rekọja lati kó awọn enia ile ọba si oke, ati lati ṣe eyiti o tọ li oju rẹ̀. Ṣimei ọmọ Gera wolẹ, o si dojubolẹ niwaju ọba, bi o ti goke odo Jordani.

Dafidi Ṣàánú Ṣimei

19 O si wi fun ọba pe, Ki oluwa mi ki o máṣe ka ẹ̀ṣẹ si mi li ọrùn, má si ṣe ranti afojudi ti iranṣẹ rẹ ṣe li ọjọ ti oluwa mi ọba jade ni Jerusalemu, ki ọba ki o má si fi si inu. 20 Nitoripe iranṣẹ rẹ mọ̀ pe on ti ṣẹ̀; si wõ, ni gbogbo idile Josefu emi li o kọ́ wá loni lati sọkalẹ wá pade oluwa mi ọba. 21 Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia dahùn o si wipe, Kò ha tọ́ ki a pa Ṣimei nitori eyi? nitoripe on ti bú ẹni-àmi-ororo Oluwa. 22 Dafidi si wipe, Ki li o wà lãrin emi ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Seruia, ti ẹ fi di ọta si mi loni? a ha le pa enia kan loni ni Israeli? o le ṣe pe emi kò mọ̀ pe, loni emi li ọba Israeli? 23 Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ kì yio kú. Ọba si bura fun u.

Dafidi Ṣàánú Mẹfiboṣẹti

24 Mefiboṣeti ọmọ Saulu si sọkalẹ lati wá pade ọba, kò wẹ ẹsẹ rẹ̀, kò si fá irungbọ̀n rẹ̀, bẹ̃ni kò si fọ aṣọ rẹ̀ lati ọjọ ti ọba ti jade titi o fi di ọjọ ti o fi pada li alafia. 25 O si ṣe, nigbati on si wá si Jerusalemu lati pade ọba, ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ kò fi ba mi lọ, Mefiboṣeti? 26 On si dahùn wipe, Oluwa mi, ọba, iranṣẹ mi li o tàn mi jẹ; nitoriti iranṣẹ rẹ ti wipe, Emi o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, emi o gùn u, emi o si tọ̀ ọba lọ, nitoriti iranṣẹ rẹ yarọ. 27 O si sọ̀rọ ibajẹ si iranṣẹ rẹ, fun oluwa mi ọba, ṣugbọn bi angeli Ọlọrun li oluwa mi ọba ri: nitorina ṣe eyi ti o dara loju rẹ. 28 Nitoripe gbogbo ile baba mi bi okú enia ni nwọn sa ri niwaju oluwa mi ọba: iwọ si fi ipò fun iranṣẹ rẹ larin awọn ti o njẹun ni ibi onjẹ rẹ. Nitorina are kili emi ni ti emi o fi ma ke pe ọba sibẹ. 29 Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nsọ ọràn rẹ siwaju mọ? emi sa ti wipe, Ki iwọ ati Siba pin ilẹ na. 30 Mefiboṣeti si wi fun ọba pe, Si jẹ ki o mu gbogbo rẹ̀, bi oluwa mi ọba ba ti pada bọ̀ wá ile rẹ̀ li alafia.

Dafidi Ṣàánú Basilai

31 Barsillai ara Gileadi si sọkalẹ lati Rogelimu wá, o si ba ọba goke odo Jordani, lati ṣe ikẹ́ rẹ̀ si ikọja odo Jordani. 32 Barsillai si jẹ arugbo ọkunrin gidigidi, ẹni ogbó ọgọrin ọdun si ni: o si pese ohun jijẹ fun ọba nigbati o ti wà ni Mahanaimu; nitoripe ọkunrin ọlọla li on iṣe. 33 Ọba si wi fun Barsillai pe, Iwọ wá ba mi goke odo, emi o si ma bọ́ ọ ni Jerusalemu. 34 Barsillai si wi fun ọba pe, Ọjọ melo ni ọdun ẹmi mi kù, ti emi o fi ba ọba goke lọ si Jerusalemu? 35 Ẹni ogbó ọgọrin ọdun sa li emi loni: emi le mọ̀ iyatọ ninu rere ati buburu? iranṣẹ rẹ le mọ̀ adùn ohun ti emi njẹ tabi ohun ti emi nmu bi? emi tun le mọ̀ adùn ohùn awọn ọkunrin ti nkọrin, ati awọn obinrin ti nkọrin bi? njẹ nitori kili iranṣẹ rẹ yio ṣe jẹ́ iyọnu sibẹ fun oluwa mi ọba? 36 Iranṣẹ rẹ yio si sin ọba lọ diẹ goke odo Jordani; ẽsi ṣe ti ọba yio fi san ẹsan yi fun mi? 37 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ pada, emi o si kú ni ilu mi, a o si sin mi ni iboji baba ati iya mi. Si wo Kimhamu iranṣẹ rẹ, yio ba oluwa mi ọba goke; iwọ o si ṣe ohun ti o ba tọ li oju rẹ fun u. 38 Ọba si dahùn wipe, Kimhamu yio ba mi goke, emi o si ṣe eyi ti o tọ loju rẹ fun u; ohunkohun ti iwọ ba si bere lọwọ mi, emi o ṣe fun ọ. 39 Gbogbo awọn enia si goke odo Jordani. Ọba si goke; ọba si fi ẹnu kò Barsillai li ẹnu, o si sure fun u; on si pada si ile rẹ̀.

Juda ati Israẹli ń Jiyàn lórí ẹni tí ó ni Ọba

40 Ọba si nlọ si Gilgali, Kimhamu si mba a lọ, gbogbo awọn enia Juda si nṣe ikẹ ọba, ati ãbọ awọn enia Israeli. 41 Si wõ, gbogbo awọn ọkunrin Israeli si tọ ọba wá, nwọn si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti awọn arakunrin wa awọn ọkunrin Juda fi ji ọ kuro, ti nwọn si fi mu ọba ati awọn ara ile rẹ̀ goke odo Jordani, ati gbogbo awọn enia Dafidi pẹlu rẹ̀. 42 Gbogbo ọkunrin Juda si da awọn ọkunrin Israeli li ohùn pe, Nitoripe ọba bá wa tan ni; ẽṣe ti ẹnyin fi binu nitori ọran yi? awa jẹ ninu onjẹ ọba rara bi? tabi o fi ẹ̀bun kan fun wa bi? 43 Awọn ọkunrin Israeli si da awọn ọkunrin Juda li ohùn pe, Awa ni ipa mẹwa ninu ọba, awa si ni ninu Dafidi jù nyin lọ, ẽṣe ti ẹnyin kò fi kà wa si, ti ìmọ wa kò fi ṣaju lati mu ọba wa pada? ọ̀rọ awọn ọkunrin Juda si le jù ọ̀rọ awọn ọkunrin Israeli lọ.

2 Samueli 20

Ọ̀tẹ̀ Ṣeba

1 Ọkunrin Beliali kan si mbẹ nibẹ orukọ rẹ̀ si njẹ Ṣeba ọmọ Bikri ara Benjamini; o si fún ipè o si wipe, Awa kò ni ipa ni Dafidi, bẹ̃li awa kò ni ini ni ọmọ Jesse: ki olukuluku ọkunrin lọ si agọ rẹ̀, ẹnyin Israeli. 2 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si lọ kuro lẹhin Dafidi, nwọn si ntọ Ṣeba ọmọ Bikri lẹhin: ṣugbọn awọn ọkunrin Juda si fi ara mọ́ ọba wọn lati odo Jordani wá titi o fi de Jerusalemu. 3 Dafidi si wá si ile rẹ̀ ni Jerusalemu; ọba si mu awọn obinrin mẹwa ti iṣe alè rẹ̀, awọn ti o ti fi silẹ lati ma ṣọ́ ile. O si há wọn mọ ile, o si mbọ́ wọn, ṣugbọn kò si tun wọle tọ̀ wọn mọ a si se wọn mọ titi di ọjọ ikú wọn, nwọn si wà bi opo. 4 Ọba si wi fun Amasa pe, Pe awọn ọkunrin Juda fun mi niwọn ijọ mẹta oni, ki iwọ na ki o si wá nihinyi. 5 Amasa si lọ lati pe awọn ọkunrin Juda: ṣugbọn o si duro pẹ jù akoko ti o fi fun u. 6 Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Nisisiyi Ṣeba ọmọ Bikri yio ṣe wa ni ibi jù ti Absalomu lọ; iwọ mu awọn iranṣẹ Oluwa rẹ, ki o si lepa rẹ̀, ki o ma ba ri ilu olodi wọ̀, ki o si bọ́ lọwọ wa, 7 Awọn ọmọkunrin Joabu si jade tọ̀ ọ lọ, ati awọn Kereti, ati awọn Peleti, ati gbogbo awọn ọkunrin alagbara: nwọn si ti Jerusalemu jade lọ, lati lepa Ṣeba ọmọ Bikri. 8 Nigbati nwọn de ibi okuta nla ti o wà ni Gibeoni, Amasa si ṣaju wọn. Joabu si di amùre si agbada rẹ̀ ti o wọ̀, o si sán idà rẹ̀ mọ idi, ninu akọ̀ rẹ̀, bi o si ti nlọ, o yọ jade. 9 Joabu si bi Amasa lere pe, Ara rẹ ko le bi, iwọ arakunrin mi? Joabu si na ọwọ́ ọtún rẹ̀ di Amasa ni irungbọ̀n mu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. 10 Ṣugbọn Amasa ko si kiyesi idà ti mbẹ li ọwọ́ Joabu: bẹ̃li on si fi gun u li ẽgun ìha ikarun, ifun rẹ̀ si tú dá silẹ, on kò si tun gún u mọ́; o si kú. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si lepa Ṣeba ọmọ Bikri. 11 Ọkan ninu awọn ọdọmọdekunrin ti o wà lọdọ Joabu si duro tì i, o si wipe, Tali ẹni ti o ba fẹran Joabu? tali o si nṣe ti Dafidi, ki o ma tọ̀ Joabu lẹhin. 12 Amasa si nyira ninu ẹ̀jẹ larin ọ̀na. ọkunrin na si ri pe gbogbo enia si duro tì i, o si gbe Amasa kuro loju ọ̀na lọ sinu ìgbẹ́, o si fi aṣọ bò o, nigbati o ti ri pe ẹnikẹni ti o ba de ọdọ rẹ̀, a duro. 13 Nigbati o si gbe e kuro li oju ọ̀na, gbogbo enia si tọ̀ Joabu lẹhin lati lepa Ṣeba ọmọ Bikri. 14 On kọja ninu gbogbo ẹya Israeli si Abeli ati si Betmaaka, ati gbogbo awọn ara Beriti; nwọn si kó ara wọn jọ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin pẹlu. 15 Nwọn wá, nwọn si do tì i ni Abeli ti Betmaaka, nwọn si mọdi tì ilu na, odi na si duro ti odi ilu na: gbogbo enia ti mbẹ lọdọ Joabu si ngbiyanju lati wó ogiri na lulẹ. 16 Obinrin ọlọgbọ́n kan si kigbe soke lati ilu na wá, pe, Fetisilẹ, fetisilẹ, emi bẹ̀ nyin, sọ fun Joabu pe, Sunmọ ihinyi emi o si ba ọ sọ̀rọ. 17 Nigbati on si sunmọ ọdọ rẹ̀, obinrin na si wipe, Iwọ ni Joabu bi? on si dahùn wipe, Emi na ni. Obinrin na si wi fun u pe, Gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ. On si dahun wipe, Emi ngbọ́. 18 O si sọ̀rọ, wipe, Nwọn ti nwi ṣaju pe niti bibere, nwọn o bere ni Abeli: bẹ̃ni nwọn si pari ọ̀ran na. 19 Emi li ọkan ninu awọn ẹni alafia ati olõtọ ni Israeli: iwọ nwá ọ̀na lati pa ilu kan run ti o jẹ iyá ni Israeli: ẽṣe ti iwọ o fi gbe ini Oluwa mì? 20 Joabu si dahùn wipe, Ki a má ri i, ki a má ri i lọdọ mi pe emi gbé mì tabi emi sì parun. 21 Ọràn na kò ri bẹ̃; ṣugbọn ọkunrin kan lati oke Efraimu, ti orukọ rẹ̀ njẹ Ṣeba, ọmọ Bikri, li o gbe ọwọ́ rẹ̀ soke si ọba, ani si Dafidi: fi on nikanṣoṣo le wa lọwọ, emi o si fi ilu silẹ. Obinrin na si wi fun Joabu pe, Wõ, ori rẹ̀ li a o si sọ si ọ lati inu odi wá. 22 Obinrin na si mu ìmọran rẹ̀ tọ gbogbo awọn enia na. Nwọn si bẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri li ori, nwọn si sọ ọ si Joabu. On si fún ipè, nwọn si tuka kuro ni ilu na, olukuluku si agọ rẹ̀. Joabu si pada lọ si Jerusalemu ati sọdọ ọba.

Àwọn adarí àwọn Òṣìṣẹ́ ní ààfin Dafidi

23 Joabu si li olori gbogbo ogun Israeli: Benaiah ọmọ Jehoiada si jẹ olori awọn Kereti, ati olori awọn Peleti: 24 Adoramu si jẹ olori awọn agbowodè: Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si jẹ akọwe nkan ti o ṣe ni ilu: 25 Ṣefa si jẹ akọwe: Sadoku ati Abiatari si li awọn alufa. 26 Ira pẹlu, ara Jairi ni nṣe alufa lọdọ Dafidi.

2 Samueli 21

Wọ́n pa àwọn Ọmọ Ọmọ Saulu

1 IYAN kan si mu ni ọjọ Dafidi li ọdun mẹta, lati ọdun de ọdun; Dafidi si bere lọdọ Oluwa, Oluwa si wipe, Nitori ti Saulu ni, ati nitori ile rẹ̀ ti o kún fun ẹ̀jẹ̀, nitoripe o pa awọn ara Gibeoni. 2 Ọba si pe awọn ara Gibeoni, o si ba wọn sọ̀rọ: awọn ara Gibeoni ki iṣe ọkan ninu awọn ọmọ Israeli, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Amori; awọn ọmọ Israeli si ti bura fun wọn: Saulu si nwá ọ̀na ati pa wọn ni itara rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli ati Juda. 3 Dafidi si bi awọn ara Gibeoni lere pe, Kili emi o ṣe fun nyin? ati kili emi o fi ṣe etutu, ki ẹnyin ki o le sure fun ilẹ ini Oluwa? 4 Awọn ara Gibeoni si wi fun u pe, Awa kò ni fi fadaka tabi wura ti Saulu ati ti idile rẹ̀ ṣe, bẹ̃ni a kò si fẹ ki ẹ pa ẹnikan ni Israeli. O si wipe, eyi ti ẹnyin ba wi li emi o ṣe. 5 Nwọn si wi fun ọba pe, ọkunrin ti o run wa, ti o si rò lati pa wa rẹ́ ki a má kù nibikibi ninu gbogbo agbegbe Israeli. 6 Mu ọkunrin meje ninu awọn ọmọ rẹ̀ fun wa, awa o si so wọn rọ̀ fun Oluwa ni Gibea ti Saulu ẹniti Oluwa ti yàn. Ọba si wipe, Emi o fi wọn fun nyin. 7 Ṣugbọn Ọba dá Mefiboṣeti si, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nitori ibura Oluwa ti o wà larin wọn, lãrin Dafidi ati Jonatani ọmọ Saulu. 8 Ọba si mu awọn ọmọkunrin mejeji ti Rispa ọmọbinrin Aia bi fun Saulu, ani Armoni ati Mefiboṣeti: ati awọn ọmọkunrin mararun ti Merabu, ọmọbinrin Saulu, awọn ti o bi fun Adrieli ọmọ Barsillai ara Meholati. 9 On si fi wọn le awọn ara Gibea lọwọ, nwọn si so wọn rọ̀ lori oke niwaju Oluwa: awọn mejeje si ṣubu lẹ̃kan, a si pa wọn ni igbà ikore, ni ibẹrẹ ikore ọka-barle. 10 Rispa ọmọbinrin Aia si mu aṣọ ọfọ̀ kan, o si tẹ́ ẹ fun ara rẹ̀ lori àpata, ni ibẹrẹ ikore, titi omi fi dà si wọn lara lati ọrun wá, kò si jẹ ki awọn ẹiyẹ oju ọrun bà le wọn li ọsan, tabi awọn ẹranko igbẹ li oru. 11 A si rò eyi, ti Rispa ọmọbinrin Aia obinrin Saulu ṣe, fun Dafidi. 12 Dafidi si lọ o si ko egungun Saulu, ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọkunrin Jabeṣi-gileadi, awọn ti o ti ji wọn kuro ni ita Betṣani, nibiti awọn Filistini gbe so wọn rọ̀, nigbati awọn Filistini pa Saulu ni Gilboa. 13 On si mu egungun Saulu ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ lati ibẹ na wá; nwọn si ko egungun awọn ti a ti so rọ̀ jọ. 14 Nwọn si sin egungun Saulu ati ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ni ilẹ Benjamini, ni Sela, ninu iboji Kiṣi baba rẹ̀: nwọn si ṣe gbogbo eyi ti ọba pa li aṣẹ: lẹhin eyini Ọlọrun si gbà ẹbẹ nitori ilẹ na.

Wọ́n Bá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun

15 Ogun si tun wà larin awọn Filistini ati Israeli; Dafidi si sọkalẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si ba awọn Filistini jà: o si rẹ̀ Dafidi. 16 Iṣbi-benobu si jẹ ọkan ninu awọn òmirán, ẹniti òṣuwọn ọ̀kọ rẹ̀ jẹ ọdunrun ṣekeli idẹ, on si sán idà titun, o si gbero lati pa Dafidi. 17 Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia si ràn a lọwọ, o si kọlu Filistini na, o si pa a. Nigbana ni awọn iranṣẹ Dafidi si bura fun u, pe, Iwọ kì yio si tun ba wa jade lọ si ibi ija mọ, ki iwọ ki o máṣe pa iná Israeli. 18 O si ṣe, lẹhin eyi, ija kan si tun wà lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini ni Gobu: nigbana ni Sibbekai ara Huṣa pa Safu, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn òmirán. 19 Ija kan si tun wà ni Gobu lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ara Betlehemu si pa arakunrin Goliati ara Gati, ẹniti ọpá ọ̀kọ rẹ̀ dabi idabú igi ti a fi hun aṣọ. 20 Ija kan si tun wà ni Gati, ọkunrin kan si wà ti o gùn pupọ, o si ni ika mẹfa li ọwọ́ kan, ati ọmọ-ẹsẹ mẹfa li ẹsẹ kan, apapọ̀ rẹ̀ si jẹ mẹrinlelogun; a si bi on na li òmirán. 21 Nigbati on si pe Israeli ni ijà, Jonatani ọmọ Ṣimei arakunrin Dafidi si pa a. 22 Awọn mẹrẹrin wọnyi li a bi li òmirán ni Gati, nwọn si ti ọwọ́ Dafidi ṣubu, ati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀.

2 Samueli 22

Orin ìṣẹ́gun tí Dafidi kọ

1 DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu. 2 O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi; 3 Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara. 4 Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. 5 Nigbati ibilu irora ikú yi mi ka kiri, ti awọn iṣàn enia buburu dẹruba mi; 6 Ọjá ipo-okú yi mi ka kiri; ikẹkun ikú ti ṣaju mi. 7 Ninu ipọnju mi emi ke pe Oluwa, emi si gbe ohùn mi soke si Ọlọrun mi: o si gbohùn mi lati tempili rẹ̀ wá, igbe mi si wọ̀ eti rẹ̀. 8 Ilẹ si mì, o si wariri; ipilẹ ọrun wariri, o si mì, nitoriti o binu. 9 Ẽfin si jade lati iho-imu rẹ̀ wa, ina lati ẹnu rẹ̀ wa si njonirun, ẹyín si nràn nipasẹ rẹ̀. 10 O tẹ ori ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ; okunkun biri-biri si mbẹ li atẹlẹsẹ rẹ̀. 11 O si gun ori kerubu, o si fò: a si ri i lori iyẹ afẹfẹ. 12 O si fi okunkun ṣe ibujoko yi ara rẹ̀ ka, ati agbajọ omi, ani iṣududu awọ sanma. 13 Nipasẹ imọlẹ iwaju rẹ̀ ẹyin-iná ràn. 14 Oluwa san ãra lati ọrun wá, ọga-ogo julọ si fọhùn rẹ̀. 15 O si ta ọfà, o si tú wọn ka; o kọ màna-mána, o si ṣẹ wọn. 16 Iṣàn ibu okun si fi ara hàn, ipilẹ aiye fi ara hàn, nipa ibawi Oluwa, nipa fifún ẽmi ihò imu rẹ̀. 17 O ranṣẹ lati oke wá, o mu mi; o fà mi jade lati inu omi nla wá. 18 O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, lọwọ awọn ti o korira mi: nitoripe nwọn li agbara jù mi lọ. 19 Nwọn ṣaju mi li ọjọ ipọnju mi; ṣugbọn Oluwa li alafẹhinti mi. 20 O si mu mi wá si àye nla: o gbà mi, nitoriti inu rẹ̀ dùn si mi. 21 Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi. 22 Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi. 23 Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn. 24 Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. 25 Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀. 26 Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo. 27 Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ. 28 Awọn enia ti o wà ninu iyà ni iwọ o si gbàla: ṣugbọn oju rẹ wà lara awọn agberaga, lati rẹ̀ wọn silẹ. 29 Nitori iwọ ni imọlẹ mi, Oluwa: Oluwa yio si sọ okunkun mi di imọlẹ. 30 Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan. 31 Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. 32 Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa? 33 Ọlọrun alagbara li o fun mi li agbara, o si sọ ọ̀na mi di titọ́. 34 O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ agbọnrin: o si mu mi duro ni ibi giga mi. 35 O kọ ọwọ́ mi ni ogun jijà; tobẹ̃ ti apá mi fà ọrun idẹ. 36 Iwọ si ti fun mi li asà igbala rẹ: irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla. 37 Iwọ si sọ itẹlẹ mi di nla li abẹ mi; tobẹ̃ ti ẹsẹ mi kò fi yọ̀. 38 Emi ti lepa awọn ọta mi, emi si ti run wọn; emi kò pẹhinda titi emi fi run wọn. 39 Emi ti pa wọn run, emi si ti fọ́ wọn, nwọn kò si le dide mọ: nwọn ṣubu labẹ ẹsẹ mi. 40 Iwọ si ti fi agbara di mi li amure fun ijà: awọn ti o ti dide si mi ni iwọ si ti tẹ̀ li ori ba fun mi. 41 Iwọ si mu awọn ọta mi pẹhindà fun mi, emi si pa awọn ti o korira mi run. 42 Nwọn wò, ṣugbọn kò si ẹnikan lati gbà wọn; nwọn wò Oluwa, ṣugbọn kò da wọn lohùn. 43 Nigbana ni emi si gun wọn wẹwẹ bi erupẹ ilẹ, emi si tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita, emi si tẹ wọn gbọrọ. 44 Iwọ si gbà mi kuro lọwọ ijà awọn enia mi, iwọ pa mi mọ ki emi ki o le ṣe olori awọn ajeji orilẹ-ède: awọn enia ti emi kò ti mọ̀ yio ma sìn mi. 45 Awọn alejo yio fi ẹ̀tan tẹriba fun mi: bi nwọn ba ti gbọ́ iró mi, nwọn o si gbọ́ ti emi. 46 Ìpaiyà yio dé bá awọn alejo, nwọn o si ma bẹ̀ru nibi kọ́lọfin wọn. 47 Oluwa mbẹ; olubukun si ni apata mi: gbigbega si li Ọlọrun apata igbala mi. 48 Ọlọrun li ẹniti ngbẹsan mi, ati ẹniti nrẹ̀ awọn enia silẹ labẹ mi. 49 On ni o gbà mi kuro lọwọ awọn ọta mi: iwọ si gbe mi soke ju awọn ti o dide si mi lọ: iwọ si gbà mi kuro lọwọ ọkunrin ìwa agbara. 50 Nitorina emi o fi ọpẹ fun ọ. Oluwa, larin awọn ajeji orilẹ-ède: emi o si kọrin si orukọ rẹ. 51 On ni ile-iṣọ igbala fun ọba rẹ̀: o si fi ãnu hàn fun ẹni-ami-ororo rẹ̀; fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ titi lailai.

2 Samueli 23

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Dafidi

1 WỌNYI si li ọ̀rọ ikẹhin Dafidi. Dafidi ọmọ Jesse, ani ọkunrin ti a ti gbega, ẹni-ami-ororo Ọlọrun Jakobu, ati olorin didùn Israeli wi pe, 2 Ẹmi Oluwa sọ ọ̀rọ nipa mi, ọ̀rọ rẹ̀ si mbẹ li ahọn mi. 3 Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun. 4 Yio si dabi imọlẹ owurọ nigbati õrun ba là, owurọ ti kò ni ikũku, nigbati koriko tutu ba hù lati ilẹ wa nipa itanṣan lẹhin òjo. 5 Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà? 6 Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Beliali yio dabi ẹgún ẹ̀wọn ti a ṣatì, nitoripe a kò le fi ọwọ́ kó wọn. 7 Ṣugbọn ọkunrin ti yio tọ́ wọn yio fi irin ati ọpa ọ̀kọ sagbàra yi ara rẹ̀ ka: nwọn o si jona lulu nibi kanna.

Àwọn Akọni Ọmọ Ogun Dafidi

8 Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin alagbara ti Dafidi ni: ẹniti o joko ni ibujoko Takmoni ni olori awọn balogun, on si ni Adino Esniti ti o pa ẹgbẹ̀rin enia lẹ̃kan. 9 Ẹniti o tẹ̀le e ni Eleasari ọmọ Dodo ara Ahohi, ọkan ninu awọn alagbara ọkunrin mẹta ti o wà pẹlu Dafidi, nigbati nwọn pe awọn Filistini ni ijà, awọn ti o kó ara wọn jọ si ibẹ lati jà, awọn ọmọkunrin Israeli si ti lọ kuro: 10 On si dide, o si kọlù awọn Filistini titi ọwọ́ fi kún u, ọwọ́ rẹ̀ si lẹ̀ mọ idà: Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla li ọjọ na; awọn enia si yipada lẹhin rẹ̀ lati ko ikogun. 11 Ẹniti o tẹ̀le e ni Samma ọmọ Agee ará Harari. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ lati piyẹ, oko kan si wà nibẹ ti o kún fun ẹwẹ: awọn enia si sa kuro niwaju awọn Filistini. 12 O si duro lagbedemeji ilẹ na, o si gbà a silẹ, o si pa awọn Filistini: Oluwa si ṣe igbala nla kan. 13 Awọn mẹta ninu ọgbọ̀n olori si sọkalẹ, nwọn si tọ Dafidi wá li akoko ikore ninu iho Adullamu: ọ̀wọ́ awọn Filistini si do ni afonifoji Refaimu. 14 Dafidi si wà ninu odi, ibudo awọn Filistini si wà ni Betlehemu nigbana. 15 Dafidi si k'ongbẹ, o wi bayi pe, Tani yio fun mi mu ninu omi kanga ti mbẹ ni Betlehemu, eyi ti o wà ni ihà ẹnu-bodè? 16 Awọn ọkunrin alagbara mẹta si la ogun awọn Filistini lọ, nwọn si fa omi lati inu kanga Betlehemu wá, eyi ti o wà ni iha ẹnu-bode, nwọn si mu tọ Dafidi wá: on kò si fẹ mu ninu rẹ̀, ṣugbọn o tú u silẹ fun Oluwa. 17 On si wipe, Ki a ma ri, Oluwa, ti emi o fi ṣe eyi; ṣe eyi li ẹ̀jẹ awọn ọkunrin ti o lọ ti awọn ti ẹmi wọn li ọwọ́? nitorina on kò si fẹ mu u. Nkan wọnyi li awọn ọkunrin alagbara mẹtẹta yi ṣe. 18 Abiṣai, arakunrin Joabu, ọmọ Seruia, on na ni pataki ninu awọn mẹta. On li o si gbe ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia, o si pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹtẹta. 19 Ọlọlajulọ li on iṣe ninu awọn mẹtẹta: o si jẹ olori fun wọn: ṣugbọn on kò to awọn mẹta iṣaju. 20 Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, on pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; o sọkalẹ pẹlu o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno. 21 O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o tó wò: ara Egipti na si ni ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn on si sọkalẹ tọ̀ ọ lọ, ton ti ọ̀pá li ọwọ́, o si gba ọ̀kọ na lọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ tirẹ̀ pa a. 22 Nkan wọnyi ni Benaia ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn ọkunrin alagbara mẹta nì. 23 Ninu awọn ọgbọ̀n na, on ṣe ọlọlajulọ, ṣugbọn on kò to awọn mẹta ti iṣaju. Dafidi si fi i ṣe igbimọ̀ rẹ̀. 24 Asaheli arakunrin Joabu si jasi ọkan ninu awọn ọgbọ̀n na; Elhanani ọmọ Dodo ti Betlehemu. 25 Ṣamma ara Harodi, Elika ara Harodi. 26 Helesi ara Palti, Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoa, 27 Abieseri ara Anetoti, Mebunnai Huṣatiti, 28 Salmoni Ahohiti, Maharai ara Netofa, 29 Helebu ọmọ Baana, ara Netofa, Ittai ọmọ Ribai ti Gibea ti awọn ọmọ Benjamini, 30 Benaia ara Piratoni, Hiddai ti afonifoji, 31 Abialboni ara Arba Asmafeti Barhumiti, 32 Eliahba ara Saalboni, Jaṣeni Gisoniti, Jonatani, 33 Ṣamma Harariti, Ahiamu ọmọ Ṣarari Harariti, 34 Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ara Maakha, Eliamu ọmọ Ahitofeli ara Giloni, 35 Hesrai ara Kermeli, Paari ara Arba, 36 Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ara Gadi, 37 Sekeli ara Ammoni, Nahari ara Beeroti, ẹniti o nru ihamọra Joabu ọmọ Seruia. 38 Ira ara Jattiri, Garebu ara Jattiri. 39 Uria ara Hitti: gbogbo wọn jẹ mẹtadilogoji.

2 Samueli 24

Dafidi Ka Àwọn Eniyan Israẹli

1 IBINU Oluwa si ru si Israeli, o si tì Dafidi si wọn, pe, Lọ kà iye Israeli ati Juda. 2 Ọba si wi fun Joabu olori ogun, ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Lọ nisisiyi si gbogbo ẹyà Israeli lati Dani titi de Beerṣeba, ki ẹ si kà iye awọn enia, ki emi le mọ̀ iye awọn enia na. 3 Joabu si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o fi kún iye awọn enia na, iyekiye ki o wu ki wọn jẹ, li ọrọrún; oju oluwa mi ọba yio si ri i: ṣugbọn ẽtiṣe ti oluwa mi ọba fi fẹ nkan yi? 4 Ṣugbọn ọ̀rọ ọba si bori ti Joabu, ati ti awọn olori ogun. Joabu ati awọn olori ogun si jade lọ kuro niwaju ọba, lati lọ ika awọn enia Israeli. 5 Nwọn si kọja odo Jordani, nwọn si pagọ ni Aroeri, ni iha apá ọtún ilu ti o wà lagbedemeji afonifoji Gadi, ati si iha Jaseri: 6 Nwọn si wá si Gileadi, ati si ilẹ Tatimhodṣi; nwọn si wá si Dan-jaani ati yikakiri si Sidoni, 7 Nwọn si wá si ilu olodi Tire, ati si gbogbo ilu awọn Hifi, ati ti awọn ara Kenaani: nwọn si jade lọ siha gusu ti Juda, ani si Beerṣeba. 8 Nwọn si la gbogbo ilẹ na ja, nwọn si wá si Jerusalemu li opin oṣù kẹsan ati ogunjọ. 9 Joabu si fi iye ti awọn enia na jasi le ọba lọwọ: o si jẹ oji ọkẹ ọkunrin alagbara ní Israeli, awọn onidà: awọn ọkunrin Juda si jẹ ọkẹ mẹ̃dọgbọn enia. 10 Ẹ̀rí ọkàn si bẹrẹ si da Dafidi lãmú lẹhin igbati o kà awọn enia na tan. Dafidi si wi fun Oluwa pe, Emi ṣẹ̀ gidigidi li eyi ti emi ṣe: ṣugbọn, emi bẹ̀ ọ, Oluwa, fi ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ jì i, nitoripe emi huwà aṣiwere gidigidi. 11 Dafidi si dide li owurọ, ọ̀rọ Oluwa si tọ Gadi wolĩ wá, ariran Dafidi, wipe, 12 Lọ, ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, emi fi nkan mẹta lọ̀ ọ; yàn ọkan ninu wọn, emi o si ṣe e si ọ. 13 Gadi si tọ Dafidi wá, o si bi i lere pe, Ki iyàn ọdun meje ki o tọ̀ ọ wá ni ilẹ rẹ bi? tabi ki iwọ ki o ma sá li oṣu mẹta niwaju awọn ọta rẹ, nigbati nwọn o ma le ọ? tabi ki arùn iparun ijọ mẹta ki o wá si ilẹ rẹ? rõ nisisiyi, ki o si mọ̀ èsi ti emi o mu pada tọ̀ ẹniti o rán mi. 14 Dafidi si wi fun Gadi pe, Iyọnu nla ba mi: jẹ ki a fi ara wa le Oluwa li ọwọ́; nitoripe ãnu rẹ̀ pọ̀: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ́. 15 Oluwa si rán arùn iparun si Israeli lati owurọ̀ titi de akoko ti a da: ẹgbã marundilogoji enia si kú ninu awọn enia na lati Dani titi fi de Beerṣeba. 16 Nigbati angeli na si nawọ́ rẹ̀ si Jerusalemu lati pa a run, Oluwa si kãnu nitori ibi na, o si sọ fun angeli ti npa awọn enia na run pe, O to: da ọwọ́ rẹ duro wayi. Angeli Oluwa na si wà nibi ipaka Arauna ara Jebusi. 17 Dafidi si wi fun Oluwa nigbati o ri angeli ti nkọlu awọn enia pe, Wõ, emi ti ṣẹ̀, emi si ti huwà buburu: ṣugbọn awọn agutan wọnyi, kini nwọn ha ṣe? jẹ ki ọwọ́ rẹ, emi bẹ̀ ọ, ki o wà li ara mi, ati li ara idile baba mi. 18 Gadi si tọ Dafidi wá li ọjọ na, o si wi fun u pe, Goke, tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa nibi ipaka Arauna ara Jebusi. 19 Gẹgẹ bi ọ̀rọ Gadi, Dafidi si goke lọ gẹgẹ bi Oluwa ti pa a li aṣẹ. 20 Arauna si wò, o si ri ọba ati awọn iranṣẹ rẹ̀ mbọ̀ wá ọdọ rẹ̀: Arauna si jade, o si wolẹ niwaju ọba o si doju rẹ̀ bolẹ. 21 Arauna si wipe, Nitori kili oluwa mi ọba ṣe tọ iranṣẹ rẹ̀ wá? Dafidi si dahùn pe, Lati rà ibi ipaka nì lọwọ rẹ, lati tẹ́ pẹpẹ kan fun Oluwa, ki arùn iparun ki o le da li ara awọn enia na. 22 Arauna si wi fun Dafidi pe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mu eyi ti o dara li oju rẹ̀, ki o si fi i rubọ: wõ, malu niyi lati fi ṣe ẹbọ sisun, ati ohun elo ipaka, ati ohun elo miran ti malu fun igi. 23 Gbogbo nkan wọnyi ni Arauna fi fun ọba, bi ọba. Arauna si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o gbà ọrẹ rẹ. 24 Ọba si wi fun Arauna pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi o rà a ni iye kan lọwọ rẹ, bi o ti wù ki o ṣe; bẹ̃li emi kì yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si Oluwa Ọlọrun mi. Dafidi si rà ibi ipaka na, ati awọn malũ na li ãdọta ṣekeli fadaka. 25 Dafidi si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ si Oluwa, o si rú ẹbọ sisun ati ti ìlaja. Oluwa si gbọ́ ẹbẹ fun ilẹ na, arùn na si da kuro ni Ìsraeli.

1 Ọba 1

Ìgbà Ogbó Dafidi

1 DAFIDI ọba si di arugbo, ọjọ rẹ̀ si pọ̀; nwọn si fi aṣọ bò o lara, ṣugbọn kò mõru. 2 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Jẹ ki a wá ọmọbinrin kan, wundia, fun Oluwa mi, ọba: ki o si duro niwaju ọba, ki o si ṣikẹ́ rẹ̀, ki o si dubulẹ li õkan-aiya rẹ̀, oluwa mi, ọba yio si mõru. 3 Nwọn si wá ọmọbinrin arẹwà kan ka gbogbo agbegbe Israeli, nwọn si ri Abiṣagi, ara Ṣunemu, nwọn si mu u tọ̀ ọba wá. 4 Ọmọbinrin na si ṣe arẹwà gidigidi, o si nṣikẹ́ ọba, o si nṣe iranṣẹ fun u; ṣugbọn ọba kò si mọ̀ ọ.

Adonija fẹ́ fi ara rẹ̀ jọba

5 Adonijah, ọmọ Haggiti, si gbe ara rẹ̀ ga, wipe, emi ni yio jọba: o si mura kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin, ati ãdọta ọkunrin lati sare niwaju rẹ̀. 6 Baba rẹ̀ kò si bà a ninu jẹ rí, pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe bayi? On si ṣe enia ti o dara gidigidi: iya rẹ̀ si bi i le Absalomu. 7 O si ba Joabu, ọmọ Seruiah, ati Abiatari, alufa gbèro: nwọn si nràn Adonijah lọwọ. 8 Ṣugbọn Sadoku alufa, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati Natani woli, ati Ṣimei, ati Rei, ati awọn ọkunrin alagbara ti mbẹ lọdọ Dafidi, kò wà pẹlu Adonijah. 9 Adonijah si pa agutan ati malu ati ẹran ọ̀sin ti o sanra nibi okuta Soheleti, ti mbẹ lẹba Enrogeli, o si pè gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ ọba, ati gbogbo ọkunrin Juda, iranṣẹ ọba: 10 Ṣugbọn Natani, alufa, ati Benaiah ati awọn ọkunrin alagbara, ati Solomoni arakunrin rẹ̀ ni kò pè.

Solomoni Jọba

11 Natani si wi fun Batṣeba, iya Solomoni pe, Iwọ kò gbọ́ pe, Adonijah, omọ Haggiti jọba, Dafidi, oluwa wa, kò si mọ̀? 12 Nitorina, wá nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, emi o si fun ọ ni ìmọ, ki iwọ ki o le gbà ẹmi rẹ là, ati ẹmi Solomoni ọmọ rẹ. 13 Lọ, ki o si tọ̀ Dafidi, ọba lọ, ki o si wi fun u pe, Ọba, oluwa mi, ṣe iwọ li o bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, ni yio jọba lẹhin mi, on ni o si joko lori itẹ mi? ẽṣe ti Adonijah fi jọba? 14 Kiyesi i, bi iwọ ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, emi o si tẹle ọ, emi o si wá ikún ọ̀rọ rẹ. 15 Batṣeba si tọ̀ ọba lọ ni iyẹ̀wu: ọba si gbó gidigidi: Abiṣagi, ara Ṣunemu, si nṣe iranṣẹ fun ọba. 16 Batṣeba si tẹriba, o si wolẹ fun ọba. Ọba si wipe, Kini iwọ nfẹ? 17 On si wi fun u pe, oluwa mi, iwọ fi Oluwa Ọlọrun rẹ bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi. 18 Sa wò o, nisisiyi, Adonijah jọba; iwọ, oluwa mi ọba, kò si mọ̀. 19 O si pa malu ati ẹran ti o li ọra, ati agùtan li ọ̀pọlọpọ, o si pe gbogbo awọn ọmọ ọba, ati Abiatari alufa, ati Joabu balogun: ṣugbọn Solomoni iranṣẹ rẹ ni kò pè. 20 Ati iwọ, oluwa mi, ọba, oju gbogbo Israeli mbẹ lara rẹ, ki iwọ ki o sọ fun wọn, tani yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀? 21 Yio si ṣe, nigbati oluwa mi ọba ba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a o si kà emi ati Solomoni ọmọ mi si ẹlẹṣẹ̀. 22 Si wò o, bi o si ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, Natani woli si wọle. 23 Nwọn si sọ fun ọba pe, Wò o, Natani woli. Nigbati o si wá siwaju ọba, o wolẹ̀, o si dojubolẹ. 24 Natani si wipe, oluwa mi, ọba! iwọ ha wipe, Adonijah ni yio jọba lẹhin mi ati pe, on o si joko lori itẹ mi bi? 25 Nitori o sọkalẹ lọ loni, o si pa malu ati ẹran ọlọra, ati agùtan li ọ̀pọ-lọpọ, o si pè gbogbo awọn ọmọ ọba, ati awọn balogun, ati Abiatari alufa; si wò o, nwọn njẹ, nwọn si nmu niwaju rẹ̀, nwọn si nwipe, Ki Adonijah ọba ki o pẹ. 26 Ṣugbọn emi, emi iranṣẹ rẹ, ati Sadoku alufa, ati Benaiah ọmọ Jehoiada, ati Solomoni, iranṣẹ rẹ, ni kò pè. 27 Nkan yi ti ọdọ oluwa mi ọba wá bi? iwọ kò si fi ẹniti yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀ hàn iranṣẹ rẹ? 28 Dafidi, ọba si dahùn o si wipe, Ẹ pè Batṣeba fun mi. On si wá siwaju ọba, o si duro niwaju ọba, 29 Ọba si bura, o si wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹniti o ti rà ọkàn mi pada kuro ninu gbogbo ìṣẹ́. 30 Gẹgẹ bi mo ti fi Oluwa, Ọlọrun Israeli bura fun ọ, wipe, Nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi ni ipò mi, bẹ̃ni emi o ṣe loni yi dandan. 31 Batṣeba si foribalẹ, o si bọ̀wọ fun ọba, o si wipe, Ki oluwa mi, Dafidi ọba ki o pẹ titi lai. 32 Dafidi ọba wipe, Ẹ pè Sadoku alufa fun mi, ati Natani woli, ati Benaiah ọmọ Jehoiada. Nwọn si wá siwaju ọba. 33 Ọba si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn iranṣẹ oluwa nyin, ki ẹ si mu ki Solomoni ọmọ mi ki o gùn ibãka mi, ki ẹ si mu sọkalẹ wá si Gihoni. 34 Ki ẹ si jẹ ki Sadoku, alufa, ati Natani woli, fi ororo yàn a nibẹ̀ li ọba lori Israeli: ki ẹ si fun fère, ki ẹ si wipe; Ki Solomoni ọba ki o pẹ! 35 Ki ẹ si goke tọ̀ ọ lẹhin, ki o si wá, ki o si joko lori itẹ mi; on o si jọba ni ipò mi: emi si pa a laṣẹ lati jẹ olori Israeli ati Juda. 36 Benaiah ọmọ Jehoiada, si da ọba lohùn, o si wipe, Amin: Oluwa, Ọlọrun ọba oluwa mi, wi bẹ̃ pẹlu. 37 Bi Oluwa ti wà pẹlu oluwa mi ọba, gẹgẹ bẹ̃ni ki o wà pẹlu Solomoni, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ oluwa mi, Dafidi ọba lọ. 38 Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti si sọkalẹ, nwọn si mu ki Solomoni ki o gùn ibãka Dafidi ọba, nwọn si mu u wá si Gihoni, 39 Sadoku alufa si mu iwo ororo lati inu agọ, o si dà a si Solomoni lori; nwọn si fun fère; gbogbo enia si wipe, Ki Solomoni ọba ki o pẹ. 40 Gbogbo enia si goke tọ̀ ọ lẹhin, awọn enia si fun ipè, nwọn si yọ̀ ayọ̀ nlanla, tobẹ̃ ti ilẹ mì fun iró wọn. 41 Ati Adonijah ati gbogbo awọn ti o pè sọdọ rẹ̀ si gbọ́, nigbati nwọn jẹun tan, Joabu si gbọ́ iró ipè o si wipe: eredi ariwo ilu ti nrọkẹkẹ yi? 42 Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufa de; Adonijah si wi fun u pe, Mã wolẹ̀; nitoripe alagbara ọkunrin ni iwọ, ati ẹniti nmu ihin-rere wá. 43 Jonatani si dahùn o si wi fun Adonijah pe, Lõtọ ni, oluwa wa, Dafidi ọba, fi Solomoni jọba. 44 Ọba si ti rán Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti pẹlu rẹ̀, nwọn si ti mu u ki o gùn ibãka ọba. 45 Sadoku, alufa ati Natani, woli si ti fi ororo yàn a li ọba ni Gihoni: nwọn si fi ayọ̀ goke lati ibẹ wá, tobẹ̃ ti ilu si nho. Eyi ni ariwo ti ẹ ti gbọ́. 46 Solomoni si joko lori itẹ ijọba pẹlu. 47 Awọn iranṣẹ ọba si wá lati sure fun oluwa wa, Dafidi ọba, pe, Ki Ọlọrun ki o mu orukọ Solomoni ki o sàn jù orukọ rẹ lọ, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ rẹ lọ. Ọba si gbadura lori akete. 48 Ọba si wi bayi pẹlu, Olubukun li Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fun mi li ẹnikan ti o joko lori itẹ mi loni, oju mi si ri i. 49 Gbogbo awọn ti a pè, ti nwọn wà li ọdọ Adonijah si bẹ̀ru, nwọn si dide, nwọn si lọ olukuluku si ọ̀na rẹ̀. 50 Adonijah si bẹ̀ru Solomoni, o si dide, o si lọ, o si di iwo pẹpẹ mu. 51 Nwọn si wi fun Solomoni pe, Wò o, Adonijah bẹ̀ru Solomoni ọba: si kiyesi i, o di iwo pẹpẹ mu, o nwipe, Ki Solomoni ọba ki o bura fun mi loni pe, On kì yio fi idà pa iranṣẹ rẹ̀. 52 Solomoni si wipe, Bi o ba jẹ fi ara rẹ̀ si ọ̀wọ, irun ori rẹ̀ kan kì yio bọ́ silẹ: ṣugbọn bi a ba ri buburu lọwọ rẹ̀, on o kú. 53 Solomoni ọba si ranṣẹ, nwọn mu u sọkalẹ lori pẹpẹ. On si wá, o si foribalẹ̀ fun Solomoni ọba: Solomoni si wi fun u pe, Mã lọ ile rẹ.

1 Ọba 2

Ìkìlọ̀ Ìkẹyìn Tí Dafidi ṣe fún Solomoni

1 ỌJỌ Dafidi si sunmọ etile ti yio kú: o si paṣẹ fun Solomoni, ọmọ rẹ̀ pe: 2 Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin. 3 Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si. 4 Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli. 5 Iwọ si mọ̀ pẹlu, ohun ti Joabu, ọmọ Seruiah, ṣe si mi, ati ohun ti o ṣe si balogun meji ninu awọn ọgagun Israeli, si Abneri, ọmọ Neri, ati si Amasa, ọmọ Jeteri, o si pa wọn, o si ta ẹ̀jẹ ogun silẹ li alafia, o si fi ẹ̀jẹ ogun si ara àmure rẹ̀ ti mbẹ li ẹ̀gbẹ rẹ̀, ati si ara salubata rẹ̀ ti mbẹ li ẹsẹ rẹ̀. 6 Nitorina, ki o ṣe gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ, ki o má si jẹ ki ewu ori rẹ̀ ki o sọkalẹ lọ si isa-okú li alafia. 7 Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ. 8 Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ. 9 Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú.

Ikú Dafidi

10 Dafidi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni ilu Dafidi. 11 Ọjọ ti Dafidi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun: ni Hebroni o jọba li ọdun meje, ni Jerusalemu o si jọba li ọdun mẹtalelọgbọn. 12 Solomoni si joko lori itẹ Dafidi baba rẹ̀; a si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ gidigidi.

Ikú Adonija

13 Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni. 14 On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi: 15 On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá. 16 Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi. 17 O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya. 18 Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ. 19 Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀. 20 On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ. 21 On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya. 22 Solomoni ọba si dahùn, o si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbere Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, kuku bere ijọba fun u pẹlu; nitori ẹgbọ́n mi ni iṣe; fun on pãpa, ati fun Abiatari, alufa, ati fun Joabu, ọmọ Seruiah. 23 Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀. 24 Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah. 25 Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú.

Wọ́n lé Abiatari kúrò ní ìlú, wọ́n sì pa Joabu

26 Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ. 27 Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo. 28 Ihin si de ọdọ Joabu: nitori Joabu ti tọ̀ Adonijah lẹhin, ṣugbọn kò tọ̀ Absalomu lẹhin: Joabu si sá sinu agọ Oluwa, o si di iwo pẹpẹ mu. 29 A si sọ fun Solomoni ọba pe, Joabu ti sá sinu agọ Oluwa; si wò o, o sunmọ pẹpẹ, Solomoni si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, pe, Lọ, ki o si kọlù u. 30 Benaiah si wá sinu agọ Oluwa, o si wi fun u pe, Bayi li ọba wi, pe, Jade wá. On si wipe, Bẹ̃kọ̀; ṣugbọn nihinyi li emi o kú. Benaiah si mu èsi fun ọba wá pe, Bayi ni Joabu wi, bayi ni o si dá mi lohùn. 31 Ọba si wi fun u pe, Ṣe gẹgẹ bi o ti wi ki o si kọlù u, ki o si sin i, ki iwọ ki o le mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lọdọ mi ati kuro lọdọ ile baba mi, ti Joabu ti ta silẹ. 32 Oluwa yio si yi ẹ̀jẹ rẹ̀ pada sori rẹ̀, nitoriti o kọlù ọkunrin meji ti o ṣe olododo, ti o sàn jù on tikararẹ̀ lọ, o si fi idà pa wọn. Dafidi baba mi kò si mọ̀, ani, Abneri, ọmọ Neri, olori ogun, ati Amasa, ọmọ Jeteri, olori ogun Juda. 33 Ẹ̀jẹ wọn yio si pada sori Joabu, ati sori iru-ọmọ rẹ̀ lailai: ṣugbọn si Dafidi ati si iru-ọmọ rẹ̀, ati si ile rẹ̀, ati si itẹ́ rẹ̀, alafia yio wà lati ọdọ Oluwa wá, 34 Benaiah, ọmọ Jehoiada, si goke, o si kọlù u, ó si pa a: a si sin i ni ile rẹ̀ li aginju. 35 Ọba si fi Benaiah, ọmọ Jehoiada, jẹ olori-ogun ni ipò rẹ̀, ati Sadoku alufa ni ọba fi si ipò Abiatari.

Ikú Ṣimei

36 Ọba si ranṣẹ, o si pe Ṣimei, o si wi fun u pe, Kọ́ ile fun ara rẹ ni Jerusalemu, ki o si ma gbe ibẹ̀, ki o má si ṣe jade lati ibẹ lọ si ibikibi. 37 Yio si ṣe li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si kọja odò Kidroni, ki iwọ mọ̀ dajudaju pe, Kikú ni iwọ o kú; ẹ̀jẹ rẹ yio wà lori ara rẹ. 38 Ṣimei si wi fun ọba pe, Ọrọ na dara, gẹgẹ bi oluwa mi ọba ti wi, bẹ̃ gẹgẹ ni iranṣẹ rẹ yio ṣe. Ṣimei si gbe Jerusalemu li ọjọ pupọ. 39 O si ṣe lẹhin ọdun mẹta, awọn ọmọ-ọdọ Ṣimei meji si lọ sọdọ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati. Nwọn si rò fun Ṣimei pe, Wo o, awọn ọmọ-ọdọ rẹ mbẹ ni Gati. 40 Ṣimei si dide, o si di kẹtẹkẹtẹ ni gari, o si lọ, o si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ bọ̀ lati Gati. 41 A si rò fun Solomoni pe, Ṣimei ti lọ lati Jerusalemu si Gati, o si pada bọ̀. 42 Ọba si ranṣẹ, o si pè Ṣimei, o si wi fun u pe, emi kò ti mu ọ fi Oluwa bura, emi kò si ti fi ọ ṣe ẹlẹri, pe, Li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si rìn jade lọ nibikibi, ki iwọ ki o mọ̀ dajudaju pe, kikú ni iwọ o kú? iwọ si wi fun mi pe, Ọrọ na ti mo gbọ́, o dara. 43 Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ? 44 Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ. 45 A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai. 46 Ọba si paṣẹ fun Benaiah ọmọ Jehoiada, o si jade lọ, o si kọlù u, o si kú. A si fi idi ijọba mulẹ li ọwọ́ Solomoni.

1 Ọba 3

Solomoni Bẹ̀bẹ̀ fún Ọgbọ́n

1 SOLOMONI si ba Farao ọba Egipti da ana, o si gbe ọmọbinrin Farao ni iyawo, o si mu u wá si ilu Dafidi, titi o fi pari iṣẹ ile rẹ̀, ati ile Oluwa, ati odi Jerusalemu yika. 2 Kiki pe, awọn enia nrubọ ni ibi giga, nitori a kò ti ikọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, titi di ọjọ wọnnì. 3 Solomoni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ̀: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si nfi turari jona ni ibi-giga. 4 Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomoni ru lori pẹpẹ na. 5 Ni Gibeoni ni Oluwa fi ara rẹ̀ hàn Solomoni loju alá li oru: Ọlọrun si wipe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ. 6 Solomoni si wipe, Iwọ ti ṣe ore nla fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi, gẹgẹ bi o ti rin niwaju rẹ li otitọ ati li ododo, ati ni iduro-ṣinṣin ọkàn pẹlu rẹ, iwọ si pa ore nla yi mọ fun u lati fun u li ọmọkunrin ti o joko lori itẹ rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri loni yi. 7 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun mi, iwọ ti fi iranṣẹ rẹ jẹ ọba ni ipo Dafidi, baba mi: ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ̀ jijade ati wiwọle. 8 Iranṣẹ rẹ si mbẹ lãrin awọn enia rẹ ti iwọ ti yàn, enia pupọ, ti a kò le moye, ti a kò si lè kà fun ọ̀pọlọpọ. 9 Nitorina, fi ọkàn imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ̀ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi? 10 Ọ̀rọ na si dara loju Oluwa, nitoriti Solomoni bère nkan yi. 11 Ọlọrun si wi fun u pe, Nitoriti iwọ bère nkan yi, ti iwọ kò si bère ẹmi gigun fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ọlá fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ẹmi awọn ọta rẹ; ṣugbọn iwọ bère oye fun ara rẹ lati mọ̀ ẹjọ-idá; 12 Wò o, emi ti ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, wò o, emi fun ọ ni ọkàn ọgbọ́n ati imoye; tobẹ̃ ti kò ti isi ẹnikan ti o dabi rẹ ṣãju rẹ, bẹ̃ni lẹhin rẹ ẹnikan kì yio dide ti yio dabi rẹ. 13 Ati eyiti iwọ kò bere, emi o fun ọ pẹlu ati ọrọ̀ ati ọlá: tobẹ̃ ti kì yio si ọkan ninu awọn ọba ti yio dabi rẹ. 14 Bi iwọ o ba si rìn ni ọ̀na mi lati pa aṣẹ ati ofin mi mọ, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ ti rìn, emi o si sún ọjọ rẹ siwaju. 15 Solomoni si jí; si wò o, alá ni. On si wá si Jerusalemu, o si duro niwaju apoti majẹmu Oluwa, o si rubọ ọrẹ sisun, o si ru ẹbọ-alafia, o si se àse fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀.

Solomoni dá ẹjọ́ kan tí Ó ta kókó

16 Nigbana ni obinrin meji, ti iṣe àgbere, wá sọdọ ọba nwọn si duro niwaju rẹ̀. 17 Ọkan ninu wọn si wipe, Jọwọ, oluwa mi, emi ati obinrin yi ngbe ile kan; emi si bi ọmọ ni ile pẹlu rẹ̀. 18 O si ṣe ni ọjọ kẹta lẹhin igbati mo bimọ tan, obinrin yi si bimọ pẹlu: awa si jumọ ngbé pọ: kò si si alejo pẹlu wa ni ile bikoṣe awa mejeji ni ile. 19 Ọmọ obinrin yi si kú li oru; nitoriti o sun le e. 20 O si dide li ọ̀ganjọ, o si gbe ọmọ mi lati iha mi, nigbati iranṣẹ-birin rẹ sun, o si tẹ́ ẹ si aiya rẹ̀, o si tẹ́ okú ọmọ tirẹ̀ si aiya mi. 21 Mo si dide li owurọ lati fi ọmú fun ọmọ mi, si wò o, o ti kú: ṣugbọn nigbati mo wò o fin li owurọ̀, si wò o, kì iṣe ọmọ mi ti mo bí. 22 Obinrin keji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi alãye ni ọmọ mi, eyi okú li ọmọ rẹ, eyi si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye si li ọmọ mi. Bayi ni nwọn nsọ niwaju ọba. 23 Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi. 24 Ọba si wipe, Ẹ mu idà fun mi wá. Nwọn si mu idà wá siwaju ọba. 25 Ọba si wipe, Ẹ là eyi alãye ọmọ si meji, ki ẹ si mu idaji fun ọkan ati idaji fun ekeji. 26 Obinrin ti eyi alãye ọmọ iṣe tirẹ̀ si wi fun ọba, nitori ti inu rẹ̀ yọ́ si ọmọ rẹ̀, o si wipe, Jọwọ, oluwa mi, ẹ fun u ni eyi alãye ọmọ, ki a máṣe pa a rara. Ṣugbọn eyi ekeji si wipe, kì yio jẹ temi tabi tirẹ, ẹ là a. 27 Ọba si dahùn o si wipe, ẹ fi alãye ọmọ fun u, ki ẹ má si ṣe pa a: on ni iya rẹ̀. 28 Gbogbo Israeli si gbọ́ idajọ ti ọba ṣe; nwọn si bẹ̀ru niwaju ọba: nitoriti nwọn ri i pe, ọgbọ́n Ọlọrun wà ninu rẹ̀, lati ṣe idajọ.

1 Ọba 4

Àwọn Òṣìṣẹ́ Solomoni

1 SOLOMONI ọba si jẹ ọba lori gbogbo Israeli. 2 Awọn wọnyi ni awọn ijoye ti o ni; Asariah, ọmọ Sadoku alufa, 3 Elihorefu ati Ahiah, awọn ọmọ Ṣiṣa li akọwe, Jehoṣafati ọmọ Ahiludi li akọwe ilu. 4 Ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, li olori-ogun: ati Sadoku ati Abiatari ni awọn alufa: 5 Ati Asariah, ọmọ Natani, li olori awọn ọgagun: Sabudu, ọmọ Natani, alufa, si ni ọrẹ ọba: 6 Ati Ahiṣari li o ṣe olori agbo-ile: ati Adoniramu, ọmọ Abda li o nṣe olori iṣẹ-irú. 7 Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese. 8 Orukọ wọn si ni wọnyi: Benhuri li oke Efraimu. 9 Bendekari ni Makasi, ati ni Ṣaalbimu ati Betṣemeṣi, ati Elonibethanani: 10 Benhesedi, ni Aruboti; tirẹ̀ ni Soko iṣe ati gbogbo ilẹ Heferi: 11 Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya. 12 Baana ọmọ Ahiludi, tirẹ̀ ni Taanaki iṣe, ati Megiddo, ati gbogbo Betṣeani ti mbẹ niha Sartana nisalẹ Jesreeli, lati Betṣeani de Abelmehola, ani titi de ibi ti mbẹ ni ikọja Jokneamu; 13 Ọmọ Geberi ni Ramoti-Gileadi; tirẹ̀ ni awọn ileto Jairi, ọmọ Manasse, ti mbẹ ni Gileadi; tirẹ̀ si ni apa Argobu, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu ti o tobi, ti o li odi ati ọpa-idabu idẹ. 14 Ahinadabu, ọmọ Iddo, li o ni Mahanaimu 15 Ahimaasi wà ni Naftali; on pẹlu li o ni Basmati, ọmọbinrin Solomoni, li aya. 16 Baana, ọmọ Huṣai wà ni Aṣeri ati ni Aloti. 17 Jehoṣafati, ọmọ Paruha, ni Issakari: 18 Ṣimei, ọmọ Ela, ni Benjamini. 19 Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na.

Ìjọba Solomoni ní ìtẹ̀síwájú ati alaafia

20 Juda ati Israeli pọ̀ gẹgẹ bi iyanrin ti mbẹ li eti okun ni ọ̀pọlọpọ, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nwọn si nṣe ariya. 21 Solomoni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti: nwọn nmu ọrẹ wá, nwọn si nsìn Solomoni ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀. 22 Onjẹ Solomoni fun ijọ kan jasi ọgbọ̀n iyẹ̀fun kikunna ati ọgọta oṣuwọn iyẹ̀fun iru miran. 23 Malu mẹwa ti o sanra, ati ogún malu lati inu papa wá, ati ọgọrun agutan, laika agbọ̀nrin, ati egbin, ati ogbúgbu, ati ẹiyẹ ti o sanra. 24 Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri. 25 Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni. 26 Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin. 27 Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù. 28 Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀. 29 Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun. 30 Ọgbọ́n Solomoni si bori ọgbọ́n gbogbo awọn ọmọ ila-õrun, ati gbogbo ọgbọ́n Egipti. 31 On si gbọ́n jù gbogbo enia; jù Etani, ara Esra, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara, awọn ọmọ Maholi: okiki rẹ̀ si kàn ni gbogbo orilẹ-ède yíka. 32 O si pa ẹgbẹdọgbọn owe: orin rẹ̀ si jẹ ẹgbẹrun o le marun. 33 O si sọ̀rọ ti igi, lati kedari ti mbẹ ni Lebanoni, ani titi de hissopu ti nhu lara ogiri: o si sọ̀ ti ẹranko pẹlu, ati ti ẹiyẹ, ati ohun ti nrako, ati ti ẹja. 34 Ẹni pupọ si wá lati gbogbo orilẹ-ède lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni; ani lati ọdọ gbogbo awọn ọba aiye, ti o gburo ọgbọ́n rẹ̀.

1 Ọba 5

Solomoni Palẹ̀mọ́ láti Kọ́ Tẹmpili

1 HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo. 2 Solomoni si ranṣẹ si Hiramu wipe, 3 Iwọ mọ̀ bi Dafidi, baba mi, kò ti le kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ nitori ogun ti o wà yi i ka kiri, titi Oluwa fi fi wọn sabẹ atẹlẹsẹ rẹ̀. 4 Ṣugbọn nisisiyi Oluwa Ọlọrun mi ti fun mi ni isimi niha gbogbo, bẹ̃ni kò si si ọta tabi ibi kan ti o ṣẹ̀. 5 Si kiye si i, mo gbèro lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun Dafidi, baba mi pe, Ọmọ rẹ, ti emi o gbe kà ori itẹ́ rẹ ni ipò rẹ, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. 6 Njẹ nisisiyi, paṣẹ ki nwọn ki o ke igi kedari fun mi lati Lebanoni wá, awọn ọmọ ọdọ mi yio si wà pẹlu awọn ọmọ ọdọ rẹ, iwọ ni emi o si sanwo ọyà awọn ọmọ ọdọ rẹ fun, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti iwọ o wi: nitoriti iwọ mọ̀ pe, kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi a ti ike igi bi awọn ara Sidoni. 7 O si ṣe, nigbati Hiramu gbọ́ ọ̀rọ Solomoni, o yọ̀ pipọ, o si wipe, Olubukún li Oluwa loni, ti o fun Dafidi ni ọmọ ọlọgbọ́n lori awọn enia pupọ yi. 8 Hiramu si ranṣẹ si Solomoni pe, Emi ti gbọ́ eyi ti iwọ ránṣẹ si mi, emi o ṣe gbogbo ifẹ rẹ niti igi kedari ati niti igi firi. 9 Awọn ọmọ ọdọ mi yio mu igi na sọkalẹ lati Lebanoni wá si okun: emi o si fi wọn ṣọwọ si ọ ni fifó li omi okun titi de ibi ti iwọ o nà ika si fun mi, emi o si mu ki nwọn ki o ko wọn sibẹ, iwọ o si ko wọn lọ: iwọ o si ṣe ifẹ mi, lati fi onjẹ fun ile mi. 10 Bẹ̃ni Hiramu fun Solomoni ni igi kedari ati igi firi gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀. 11 Solomoni si fun Hiramu ni ẹgbãwa oṣuwọ̀n ọkà ni onjẹ fun ile rẹ̀, ati ogún oṣuwọ̀n ororo daradara; bẹ̃ni Solomoni nfi fun Hiramu li ọdọdun. 12 Oluwa si fun Solomoni li ọgbọ́n gẹgẹ bi o ti wi fun u: alafia si wà lãrin Hiramu ati Solomoni; awọn mejeji si ṣe adehùn. 13 Solomoni ọba, si ṣà asìnrú enia jọ ni gbogbo Israeli; awọn asìnrú na jẹ ẹgbã mẹdogun enia. 14 O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na. 15 Solomoni si ni ẹgbã marundilogoji enia ti nru ẹrù, ọkẹ mẹrin gbẹnagbẹna lori oke; 16 Laikà awọn ijoye ninu awọn ti a fi ṣe olori iṣẹ Solomoni, ẹgbẹrindilogun o le ọgọrun enia, ti o nṣe alaṣẹ awọn enia ti nṣisẹ na. 17 Ọba si paṣẹ, nwọn si mu okuta wá, okuta iyebiye, ati okuta gbígbẹ lati fi ipilẹ ile na le ilẹ. 18 Awọn akọle Solomoni, ati awọn akọle Hiramu si gbẹ́ wọn, ati awọn ara Gebali: nwọn si pèse igi ati okuta lati kọ́ ile na.

1 Ọba 6

Solomoni kọ́ Tẹmpili

1 O si ṣe, ni ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹ̀rẹ si ikọ́ ile fun Oluwa. 2 Ile na ti Solomoni ọba kọ́ fun Oluwa, gigun rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ibú rẹ̀, ogun igbọnwọ, ati giga rẹ̀, ọgbọn igbọnwọ. 3 Ati ọ̀dẹdẹ niwaju tempili ile na, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, gẹgẹ bi ibú ile na: igbọnwọ mẹwa si ni ibú rẹ̀ niwaju ile na. 4 Ati fun ile na ni a ṣe ferese fun síse. 5 Lara ogiri ile na li o bù yàra yika; ati tempili, ati ibi-mimọ́-julọ, li o si ṣe yara yika. 6 Yara isalẹ, igbọnwọ marun ni gbigbòro rẹ̀, ti ãrin, igbọnwọ mẹfa ni gbigbòro rẹ̀, ati ẹkẹta, igbọnwọ meje ni gbigbòro rẹ̀, nitori lode ogiri ile na li o dín igbọnwọ kọ̃kan kakiri, ki igi-àja ki o má ba wọ inu ogiri ile na. 7 Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ. 8 Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta. 9 Bẹ̃li o kọ́ ile na, ti o si pari rẹ̀: o si fi gbelerù ati apako kedari bò ile na. 10 O si kọ́ yara gbè gbogbo ile na, igbọnwọ marun ni giga: o fi ìti kedari mú wọn fi ara ti ile na. 11 Ọ̀rọ Oluwa si tọ Solomoni wá wipe, 12 Nipa ti ile yi ti iwọ nkọ́ lọwọ nì, bi iwọ o ba rin ninu aṣẹ mi, ti iwọ o si ṣe idajọ mi, ati ti iwọ o si pa gbogbo ofin mi mọ lati ma rin ninu wọn, nigbana ni emi o mu ọ̀rọ mi ṣẹ pẹlu rẹ, ti mo ti sọ fun Dafidi, baba rẹ; 13 Emi o si ma gbe ãrin awọn ọmọ Israeli, emi kì o si kọ̀ Israeli, enia mi. 14 Solomoni si kọ́ ile na, o si pari rẹ̀.

Àrà tí Solomoni dá sinu tẹmpili náà

15 O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na. 16 O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ. 17 Ati ile na, eyini ni Tempili niwaju rẹ̀, jẹ ogoji igbọnwọ ni gigùn. 18 Ati kedari ile na ninu ile li a fi irudi ati itanna ṣe iṣẹ ọnà rẹ̀: gbogbo rẹ̀ kiki igi kedari; a kò ri okuta kan. 19 Ibi-mimọ́-julọ na li o mura silẹ ninu ile lati gbe apoti majẹmu Oluwa kà ibẹ. 20 Ibi-mimọ́-julọ na si jasi ogún igbọnwọ ni gigùn, li apa ti iwaju, ati ogún igbọnwọ ni ibú, ati ogún igbọnwọ ni giga rẹ̀; o si fi wura ailadàlu bò o, bẹ̃li o si fi igi kedari bò pẹpẹ. 21 Solomoni si fi wura ailadàlu bò ile na ninu: o si fi ẹwọ́n wura ṣe oju ibi-mimọ́-julọ, o si fi wura bò o. 22 Gbogbo ile na li o si fi wura bò titi o fi pari gbogbo ile na; ati gbogbo pẹpẹ ti o wà niha ibi-mimọ́-julọ li o fi wura bò. 23 Ati ninu ibi-mimọ́-julọ li o fi igi olifi ṣe kerubu meji, ọkọkan jẹ igbọnwọ mẹwa ni giga. 24 Ati igbọnwọ marun ni apa kerubu kan, ati igbọnwọ marun ni apa kerubu keji; lati igun apakan titi de igun apa-keji jẹ igbọnwọ mẹwa. 25 Igbọnwọ mẹwa si ni kerubu keji: kerubu mejeji jẹ ìwọn kanna ati titobi kanna. 26 Giga kerubu kan jẹ igbọnwọ mẹwa, bẹ̃ni ti kerubu keji. 27 O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na. 28 O si fi wura bò awọn kerubu na. 29 O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode. 30 Ilẹ ile na li o fi wura tẹ́ ninu ati lode. 31 Ati fun oju-ọ̀na ibi-mimọ́-julọ li o ṣe ilẹkùn igi olifi: itẹrigbà ati opó ihà jẹ idamarun ogiri. 32 Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ. 33 Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na. 34 Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po. 35 O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́. 36 O si fi ẹsẹsẹ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ẹsẹ kan ìti kedari kọ́ agbala ti inu ọhun. 37 Li ọdun kẹrin li a fi ipilẹ ile Oluwa le ilẹ̀, li oṣu Sifi. 38 Ati li ọdun kọkanla, li oṣu Bulu, ti iṣe oṣu kẹjọ, ni ile na pari jalẹ-jalẹ, pẹlu gbogbo ipin rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o yẹ: o si fi ọdun meje kọ́ ọ.

1 Ọba 7

Ààfin Solomoni

1 ṢUGBỌN Solomoni fi ọdun mẹtala kọ́ ile on tikararẹ̀, o si pari gbogbo iṣẹ ile rẹ̀. 2 O kọ́ ile-igbó Lebanoni pẹlu; gigùn rẹ̀ jasi ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ adọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọnwọ, lori ọ̀wọ́ mẹrin opó igi kedari, ati idabu igi kedari lori awọn opó na. 3 A si fi igi kedari tẹ́ ẹ loke lori iyara ti o joko lori ọwọ̀n marunlelogoji, mẹdogun ni ọ̀wọ́. 4 Ferese si wà ni ọ̀wọ́ mẹta, oju si ko oju ni ọ̀na mẹta. 5 Gbogbo ilẹkun ati opó si dọgba ni igun mẹrin; oju si ko oju ni ọ̀na mẹta. 6 O si fi ọwọ̀n ṣe iloro: gigùn rẹ̀ jẹ adọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ ọgbọ̀n igbọnwọ, iloro kan si wà niwaju rẹ̀: ani ọwọ̀n miran, igi itẹsẹ ti o nipọn si mbẹ niwaju wọn. 7 O si ṣe iloro itẹ nibiti yio ma ṣe idajọ, ani iloro idajọ: a si fi igi kedari tẹ ẹ lati iha kan de keji. 8 Ile rẹ̀ nibiti o ngbe, ni agbala lẹhin ile titi de ọ̀dẹdẹ, si jẹ iṣẹ kanna. Solomoni si kọ́ ile fun ọmọbinrin Farao, ti o ni li aya, bi iloro yi. 9 Gbogbo wọnyi jẹ okuta iyebiye gẹgẹ bi iwọn okuta gbigbẹ́, ti a fi ayùn rẹ́ ninu ati lode, ani lati ipilẹ de ibori-oke ile, bẹ̃ si ni lode si apa agbala nla. 10 Ipilẹ na jẹ okuta iyebiye, ani okuta nlanla, okuta igbọnwọ mẹwa, ati okuta igbọnwọ mẹjọ. 11 Ati okuta iyebiye wà loke nipa iwọ̀n okuta ti a gbẹ́, ati igi kedari. 12 Ati agbàla nla yikakiri pẹlu jẹ ọ̀wọ́ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ọ̀wọ́ kan igi idabu ti kedari, ati fun agbala ile Oluwa ti inu lọhun, ati fun iloro ile na.

Iṣẹ́ Huramu

13 Solomoni ọba si ranṣẹ, o si mu Hiramu lati Tire wá. 14 Ọmọkunrin opó kan ni, lati inu ẹya Naftali, baba rẹ̀ si ṣe ara Tire, alagbẹdẹ idẹ: on si kún fun ọgbọ́n, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ. O si tọ̀ Solomoni ọba wá, o si ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀.

Òpó Bàbà Meji

15 O si dà ọwọ̀n idẹ meji, igbọnwọ mejidilogun ni giga ọkọkan: okùn igbọnwọ mejila li o si yi ọkọkan wọn ka. 16 O si ṣe ipari meji ti idẹ didà lati fi soke awọn ọwọ̀n na: giga ipari kan jẹ igbọnwọ marun, ati giga ipari keji jẹ igbọnwọ marun: 17 Ati oniruru iṣẹ, ati ohun wiwun iṣẹ ẹ̀wọn fun awọn ipari ti mbẹ lori awọn ọwọ̀n na; meje fun ipari kan, ati meje fun ipari keji. 18 O si ṣe awọn pomegranate ani ọ̀wọ́ meji yikakiri lara iṣẹ àwọn na, lati fi bò awọn ipari ti mbẹ loke: bẹ̃li o si ṣe fun ipari keji. 19 Ati ipari ti mbẹ li oke awọn ọwọ̀n ti mbẹ ni ọ̀dẹdẹ na ti iṣẹ lili, ni igbọnwọ mẹrin. 20 Ati awọn ipari lori ọwọ̀n meji na wà loke: nwọn si sunmọ ibi ti o yọ lara ọwọ̀n ti o wà nibi iṣẹ àwọn: awọn pomegranate jẹ igba ni ọ̀wọ́ yikakiri, lori ipari keji. 21 O si gbe awọn ọwọ̀n na ro ni iloro tempili: o si gbe ọwọ̀n ọ̀tun ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Jakini: o si gbe ọwọ̀n òsi ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Boasi. 22 Lori oke awọn ọwọ̀n na ni iṣẹ lili wà; bẽni iṣẹ ti awọn ọwọ̀n si pari.

Agbada Bàbà

23 O si ṣe agbada nla didà igbọnwọ mẹwa lati eti kan de ekeji: o ṣe birikiti, giga rẹ̀ si jẹ igbọnwọ marun: okùn ọgbọ̀n igbọnwọ li o si yi i kakiri. 24 Ati nisalẹ eti rẹ̀ yikakiri kóko wà yi i ka, mẹwa ninu igbọnwọ kan, o yi agbada nla na kakiri: a dà kóko na ni ẹsẹ meji, nigbati a dà a. 25 O duro lori malu mejila, mẹta nwo iha ariwa, mẹta si nwo iwọ-õrun, mẹ̃ta si nwo gusu, mẹta si nwo ila-õrun; agbada nla na si joko lori wọn, gbogbo apa ẹhin wọn si mbẹ ninu. 26 O si nipọn to ibú atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà ẹgbã iwọ̀n Bati.

Ọkọ̀ Bàbà

27 O si ṣe ijoko idẹ mẹwa; igbọnwọ mẹrin ni gigùn ijoko kọkan, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ mẹta ni giga rẹ̀. 28 Iṣẹ awọn ijoko na ri bayi: nwọn ni alafo ọ̀na arin, alafo ọ̀na arin na si wà lagbedemeji ipade eti. 29 Ati lara alafo ọ̀na arin ti mbẹ lagbedemeji ni aworan kiniun, malu, ati awọn kerubu wà; ati lori ipade eti, ijoko kan wà loke: ati labẹ awọn kiniun, ati malu ni iṣẹ ọṣọ́ wà. 30 Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na. 31 Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika. 32 Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ. 33 Iṣẹ ayika-kẹkẹ́ na si dabi iṣẹ kẹkẹ́; igi idalu wọn, ati ibi iho, ati ibi ipade, ati abukala wọn, didà ni gbogbo wọn. 34 Ifẹsẹtẹ mẹrin li o wà fun igun mẹrin ijoko na: ifẹsẹtẹ na si jẹ ti ijoko tikararẹ̀ papã. 35 Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna. 36 Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri. 37 Gẹgẹ bayi li o si ṣe awọn ijoko mẹwẹwa: gbogbo wọn li o si ni didà kanna, iwọ̀n kanna ati titobi kanna. 38 O si ṣe agbada idẹ mẹwa: agbada kan gbà to òji iwọn Bati: agbada kọ̃kan si jẹ igbọnwọ mẹrin: lori ọkọ̃kan ijoko mẹwẹwa na ni agbada kọ̃kan wà. 39 O si fi ijoko marun si apa ọtún ile na, ati marun si apa òsi ile na: o si gbe agbada-nla ka apa ọ̀tún ile na, si apa ila-õrun si idojukọ gusu:

Ìṣírò àwọn ohun èlò tí ó wà ninu ilé OLUWA

40 Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba: 41 Ọwọ̀n meji, ati ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n meji; ati iṣẹ àwọ̀n meji lati bò ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n; 42 Ati irinwo pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n meji, ọ̀wọ́ meji pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n kan, lati bò awọn ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n; 43 Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na. 44 Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ agbada nla. 45 Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan. 46 Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ ti mbẹ lagbedemeji Sukkoti on Sartani. 47 Solomoni si jọwọ gbogbo ohun-elo na silẹ li alaiwọ̀n, nitori ti nwọn papọju: bẹ̃ni a kò si mọ̀ iwọ̀n idẹ na. 48 Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Oluwa: pẹpẹ wura, ati tabili wura, lori eyi ti akara ifihan gbe wà. 49 Ati ọpa fitila wura daradara, marun li apa ọtún ati marun li apa òsi, niwaju ibi mimọ́-julọ, pẹlu itanna eweko, ati fitila, ati ẹ̀mú wura. 50 Ati ọpọ́n, ati alumagaji-fitila, ati awo-koto, ati ṣibi, ati awo turari ti wura daradara; ati agbekọ wura, fun ilẹkun inu ile, ibi mimọ́-julọ, ati fun ilẹkun ile na, ani ti tempili. 51 Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ọba ṣe fun ile Oluwa pari. Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá; fadaka, ati wura, ati ohun-elo, o si fi wọn sinu iṣura ile Oluwa.

1 Ọba 8

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí wá sí inú Tẹmpili

1 NIGBANA ni Solomoni papejọ awọn agba Israeli, ati gbogbo awọn olori awọn ẹ̀ya, awọn olori awọn baba awọn ọmọ Israeli, si ọdọ Solomoni ọba ni Jerusalemu, ki nwọn ki o lè gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá lati ilu Dafidi, ti iṣe Sioni. 2 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pe ara wọn jọ si ọdọ Solomoni ọba ni ajọ ọdun ni oṣu Etanimu, ti iṣe oṣu keje. 3 Gbogbo awọn agbàgba Israeli si wá, awọn alufa si gbe apoti-ẹri. 4 Nwọn si gbe apoti-ẹ̀ri Oluwa wá soke, ati agọ ajọ enia, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ ani nkan wọnni ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi gbe goke wá. 5 Ati Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀ niwaju apoti-ẹri, nwọn nfi agutan ati malu ti a kò le mọ̀ iye, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ rubọ. 6 Awọn alufa si gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀ sinu ibi-idahùn ile na, ni ibi mimọ́-julọ labẹ iyẹ awọn kerubu. 7 Nitori awọn kerubu nà iyẹ wọn mejeji si ibi apoti-ẹri, awọn kerubu na si bò apọti-ẹri ati awọn ọpá rẹ̀ lati oke wá. 8 Nwọn si fa awọn ọpá na jade tobẹ̃ ti a nfi ri ori awọn ọpá na lati ibi mimọ́ niwaju ibi-idahùn, a kò si ri wọn lode: nibẹ ni awọn si wà titi di oni yi. 9 Kò si nkankan ninu apoti-ẹri bikoṣe tabili okuta meji, ti Mose ti fi si ibẹ ni Horebu nigbati Oluwa ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti ilẹ Egipti jade. 10 O si ṣe, nigbati awọn alufa jade lati ibi mimọ́ wá, awọsanma si kún ile Oluwa. 11 Awọn alufa kò si le duro ṣiṣẹ nitori awọsanma na: nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa. 12 Nigbana ni Solomoni sọ pe: Oluwa ti wi pe, on o mã gbe inu okùnkun biribiri. 13 Nitõtọ emi ti kọ́ ile kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀, ibukojo kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀ titi lai.

Ọ̀rọ̀ tí Solomoni bá àwọn eniyan sọ

14 Ọba si yi oju rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ enia Israeli: gbogbo ijọ enia Israeli si dide duro; 15 O si wipe, Ibukún ni fun Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ fun Dafidi, baba mi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ mu u ṣẹ, wipe, 16 Lati ọjọ ti emi ti mu Israeli, awọn enia mi jade kuro ni Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹyà Israeli lati kọ́ ile kan, ki orukọ mi ki o le mã gbe inu rẹ̀: ṣugbọn emi yàn Dafidi ṣe olori Israeli, awọn enia mi. 17 O si wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli. 18 Oluwa si wi fun Dafidi baba mi pe, Bi o tijẹpe o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile kan fun orukọ mi, iwọ ṣe rere ti o fi wà li ọkàn rẹ. 19 Ṣibẹ̀ iwọ kì yio kọ́ ile na, ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio ti inu rẹ jade, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. 20 Oluwa si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ, emi si dide ni ipò Dafidi, baba mi, mo si joko lori itẹ́ Israeli, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, emi si kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli. 21 Emi si ti ṣe àye kan nibẹ̀ fun apoti-ẹri, ninu eyiti majẹmu Oluwa gbe wà, ti o ti ba awọn baba wa dá, nigbati o mu wọn jade lati ilẹ Egipti wá.

Adura Solomoni

22 Solomoni si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, loju gbogbo ijọ enia Israeli, o si nà ọwọ́ rẹ̀ mejeji soke ọrun: 23 O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ãnu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti nfi gbogbo ọkàn wọn rin niwaju rẹ: 24 Ẹniti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ: iwọ fi ẹnu rẹ sọ pẹlu, o si ti fi ọwọ́ rẹ mu u ṣẹ, gẹgẹ bi o ti ri loni. 25 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́ wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ Israeli; kiki bi awọn ọmọ rẹ ba le kiyesi ọ̀na wọn, ki nwọn ki o mã rìn niwaju mi gẹgẹ bi iwọ ti rìn niwaju mi. 26 Njẹ nisisiyi, Ọlọrun Israeli, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ, emi bẹ̀ ọ, ti iwọ ti sọ fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi. 27 Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́? 28 Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni: 29 Ki oju rẹ lè ṣi si ile yi li ọsan ati li oru, ani si ibi ti iwọ ti wipe: Orukọ mi yio wà nibẹ: ki iwọ ki o lè tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ yio gbà si ibi yi. 30 Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì. 31 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi: 32 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀. 33 Nigbati a ba lù Israeli, enia rẹ bòlẹ niwaju awọn ọ̀ta, nitoriti nwọn dẹṣẹ si ọ, ti nwọn ba si yipada si ọ, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ ni ile yi: 34 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli, enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn. 35 Nigbati a ba sé ọrun mọ, ti kò si òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ: bi nwọn ba gbadura si iha ibi yi, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, bi nwọn ba si yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nigbati iwọ ba pọ́n wọn li oju. 36 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jì, ati ti Israeli, enia rẹ, nigbati o kọ́ wọn li ọ̀na rere ninu eyiti nwọn iba mã rin, ki o si rọ̀ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun enia rẹ ni ilẹ-ini. 37 Bi iyàn ba mu ni ilẹ, bi ajakalẹ-arùn ni, tabi ìrẹdanu, tabi bibu, tabi bi ẽṣu tabi bi kòkorò ti njẹrun ba wà; bi ọtá wọn ba dó tì wọn ni ilẹ ilu wọn; ajakalẹ-arùn gbogbo, arùn-ki-arun gbogbo. 38 Adura ki adura, ati ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ, ti a ba ti ọdọ ẹnikan tabi lati ọdọ gbogbo Israeli, enia rẹ gbà, ti olukuluku yio mọ̀ ibanujẹ ọkàn ara rẹ̀, bi o ba si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mejeji si iha ile yi! 39 Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ, ki o si darijì, ki o si ṣe ki o si fun olukulùku enia gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ọkàn ẹniti iwọ mọ̀; nitoriti iwọ, iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn gbogbo awọn ọmọ enia; 40 Ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa. 41 Pẹlupẹlu, niti alejò, ti kì iṣe ti inu Israeli enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okerè jade wá nitori orukọ rẹ. 42 Nitoriti nwọn o gbọ́ orukọ nla rẹ, ati ọwọ́ agbára rẹ, ati ninà apa rẹ; nigbati on o wá, ti yio si gbadura si iha ile yi; 43 Iwọ gbọ́ li ọrun, ibùgbe rẹ, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejò na yio ke pè ọ si: ki gbogbo aiye ki o lè mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ, gẹgẹ bi Israeli, enia rẹ, ki nwọn ki o si lè mọ̀ pe: orukọ rẹ li a fi npè ile yi ti mo kọ́. 44 Bi enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọtá wọn, li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, bi nwọn ba si gbadura si Oluwa siha ilu ti iwọ ti yàn, ati siha ile ti mo kọ́ fun orukọ rẹ. 45 Nigbana ni ki o gbọ́ adura wọn, ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun, ki o si mu ọràn wọn duro. 46 Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ, nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọta, tobẹ̃ ti a si kó wọn lọ ni igbèkun si ilẹ ọta, jijìna tabi nitosi; 47 Bi nwọn ba rò inu ara wọn wò ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn ba si ronupiwàda, ti nwọn ba si bẹ̀ ọ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe ohun ti kò tọ, awa ti ṣe buburu; 48 Bi nwọn ba si fi gbogbo àiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ ni ilẹ awọn ọta wọn, ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn si gbadura si ọ siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ilu ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi kọ́ fun orukọ rẹ: 49 Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun ibugbe rẹ, ki o si mu ọ̀ran wọn duro: 50 Ki o si darijì awọn enia rẹ ti o ti dẹṣẹ si ọ, ati gbogbo irekọja wọn ninu eyiti nwọn ṣẹ̀ si ọ, ki o si fun wọn ni ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ki nwọn ki o le ṣãnu fun wọn. 51 Nitori enia rẹ ati ini rẹ ni nwọn, ti iwọ mu ti Egipti jade wá, lati inu ileru irin: 52 Ki oju rẹ ki o le ṣi si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati si ẹ̀bẹ Israeli enia rẹ, lati tẹtisilẹ si wọn ninu ohun gbogbo ti nwọn o ke pè ọ si. 53 Nitoriti iwọ ti yà wọn kuro ninu gbogbo orilẹ-ède aiye, lati mã jẹ ini rẹ, bi iwọ ti sọ lati ọwọ Mose iranṣẹ rẹ, nigbati iwọ mu awọn baba wa ti Egipti jade wá, Oluwa Ọlọrun.

Adura Ìparí

54 O si ṣe, bi Solomoni ti pari gbigbà gbogbo adura ati ẹ̀bẹ yi si Oluwa, o dide kuro lori ikunlẹ ni ẽkún rẹ̀ niwaju pẹpẹ Oluwa pẹlu titẹ́ ọwọ rẹ̀ si oke ọrun. 55 O si dide duro, o si fi ohùn rara sure fun gbogbo ijọ enia Israeli wipe, 56 Ibukún ni fun Oluwa ti o ti fi isimi fun Israeli enia rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ṣe ileri: kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo ileri rere rẹ̀ ti o ti ṣe lati ọwọ Mose, iranṣẹ rẹ̀ wá. 57 Oluwa Ọlọrun wa ki o wà pẹlu wa, bi o ti wà pẹlu awọn baba wa: ki o má fi wa silẹ, ki o má si ṣe kọ̀ wa silẹ; 58 Ṣugbọn ki o fa ọkàn wa si ọdọ ara rẹ̀, lati ma rin ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ti o ti paṣẹ fun awọn baba wa. 59 Ki o si jẹ ki ọ̀rọ mi wọnyi, ti mo fi bẹ̀bẹ niwaju Oluwa, ki o wà nitosi, Oluwa Ọlọrun wa, li ọsan ati li oru, ki o le mu ọ̀ran iranṣẹ rẹ duro, ati ọ̀ran ojojumọ ti Israeli, enia rẹ̀. 60 Ki gbogbo enia aiye le mọ̀ pe, Oluwa on li Ọlọrun, kò si ẹlomiran. 61 Nitorina, ẹ jẹ ki aìya nyin ki o pé pẹlu Oluwa Ọlọrun wa, lati mã rìn ninu aṣẹ rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, bi ti oni yi.

Yíya ilé OLUWA sí mímọ́

62 Ati ọba, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ru ẹbọ niwaju Oluwa. 63 Solomoni si ru ẹbọ ọrẹ-alafia, ti o ru si Oluwa, ẹgbã-mọkanla malu, ati ọkẹ mẹfa àgutan. Bẹ̃ni ọba ati gbogbo awọn ọmọ Israeli yà ile Oluwa si mimọ́. 64 Li ọ̀jọ na ni ọba yà agbàla ãrin ti mbẹ niwaju ile Oluwa si mimọ́: nitori nibẹ ni o ru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ọrẹ-onjẹ, ati ẹbọ-ọpẹ: nitori pẹpẹ idẹ ti mbẹ niwaju Oluwa kere jù lati gba ọrẹ-sisun ati ọrẹ-ọnjẹ, ati ọ̀ra ẹbọ-ọpẹ. 65 Ati li àkoko na, Solomoni papejọ kan, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ajọ nla-nlã ni, lati iwọ Hamati titi de odò Egipti, niwaju Oluwa Ọlọrun wa, ijọ meje on ijọ meje, ani ijọ mẹrinla. 66 Li ọjọ kẹjọ o rán awọn enia na lọ: nwọn si sure fun ọba, nwọn si lọ sinu agọ wọn pẹlu ayọ̀ ati inu-didun, nitori gbogbo ore ti Oluwa ti ṣe fun Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fun Israeli, enia rẹ̀.

1 Ọba 9

Ọlọrun tún fara han Solomoni

1 O si ṣe, bi Solomoni ti pari kikọ́ ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ifẹ Solomoni ti o wù u lati ṣe, 2 Oluwa fi ara hàn Solomoni li ẹrinkeji, gẹgẹ bi o ti fi ara hàn a ni Gibeoni. 3 Oluwa si wi fun u pe, Mo ti gbọ́ adura rẹ ati ẹ̀bẹ rẹ, ti iwọ ti bẹ̀ niwaju mi, mo ti ya ile yi si mimọ́, ti iwọ ti kọ́, lati fi orukọ mi sibẹ titi lai; ati oju mi ati ọkàn mi yio wà nibẹ titi lai. 4 Bi iwọ o ba rìn niwaju mi: bi Dafidi baba rẹ ti rìn, ni otitọ ọkàn, ati ni iduroṣinṣin, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, ti iwọ o si pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́: 5 Nigbana li emi o fi idi itẹ́ ijọba rẹ mulẹ lori Israeli titi lai, bi mo ti ṣe ileri fun Dafidi baba rẹ, wipe, Iwọ kì yio fẹ ọkunrin kan kù lori itẹ́ Israeli. 6 Ṣugbọn bi ẹnyin o ba yipada lati mã tọ̀ mi lẹhin, ẹnyin, tabi awọn ọmọ nyin, bi ẹnyin kò si pa ofin mi mọ́, ati aṣẹ mi ti mo ti fi si iwaju nyin, ṣugbọn bi ẹ ba lọ ti ẹ si sìn awọn ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn: 7 Nigbana ni emi o ké Israeli kuro ni ilẹ ti emi fi fun wọn; ati ile yi, ti mo ti yà si mimọ́ fun orukọ mi li emi o gbe sọnù kuro niwaju mi; Israeli yio si di owe ati ifiṣẹsin lãrin gbogbo orilẹ-ède. 8 Ati ile yi, ti o ga, ẹnu o si ya olukuluku ẹniti o kọja lẹba rẹ̀, yio si pòṣe: nwọn o si wipe; ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi ati si ile yi? 9 Nwọn o si dahùn wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, ẹniti o mu awọn baba wọn jade ti ilẹ Egipti wá, nwọn gbá awọn ọlọrun miran mú, nwọn si bọ wọn, nwọn si sìn wọn: nitorina ni Oluwa ṣe mu gbogbo ibi yi wá sori wọn.

Solomoni ṣe Àdéhùn pẹlu Hiramu Ọba

10 O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba. 11 Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili. 12 Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u. 13 On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi. 14 Hiramu si fi ọgọta talenti wura ranṣẹ si ọba.

Àwọn Nǹkan pataki mìíràn tí Solomoni ṣe

15 Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri. 16 Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ. 17 Solomoni si kọ́ Geseri, ati Bethoroni-isalẹ. 18 Ati Baalati, ati Tadmori ni aginju, ni ilẹ na. 19 Ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati ilu kẹkẹ́ rẹ̀, ati ilu fun awọn ẹlẹsin rẹ̀, ati eyiti Solomoni nfẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni, ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀. 20 Gbogbo enia ti o kù ninu awọn ara Amori, ara Hitti, Perisi, Hifi ati Jebusi, ti kì iṣe ti inu awọn ọmọ Israeli. 21 Awọn ọmọ wọn ti o kù lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò le parun tũtu, awọn ni Solomoni bù iṣẹ-iru fun titi di oni yi. 22 Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli, Solomoni kò fi ṣe ẹrú, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ologun ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn balogun rẹ̀, ati awọn olori kẹkẹ́ rẹ̀ ati ti awọn ẹlẹsin rẹ̀. 23 Awọn wọnyi ni awọn olori olutọju ti mbẹ lori iṣẹ Solomoni, ãdọta-dilẹgbẹta, ti nṣe akoso lori awọn enia ti nṣe iṣẹ na. 24 Ṣugbọn ọmọbinrin Farao goke lati ilu Dafidi wá si ile rẹ̀, ti Solomoni kọ́ fun u: nigbana ni o kọ́ Millo. 25 Ati nigba mẹta li ọdun ni Solomoni iru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ẹbọ-ọpẹ lori pẹpẹ ti o tẹ́ fun Oluwa, o si sun turari lori eyi ti mbẹ niwaju Oluwa. Bẹ̃li o pari ile na. 26 Solomoni ọba si sẹ ọ̀wọ-ọkọ̀ ni Esioni-Geberi, ti mbẹ li ẹba Eloti, leti Okun-pupa ni ilẹ Edomu. 27 Hiramu si rán awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn atukọ ti o ni ìmọ okun, pẹlu awọn iranṣẹ Solomoni ninu ọ̀wọ-ọkọ̀ na. 28 Nwọn si de Ofiri, nwọn si mu wura lati ibẹ wá, irinwo talenti o le ogun, nwọn si mu u fun Solomoni ọba wá.

1 Ọba 10

Ìbẹ̀wò Ọbabinrin Ìlú Ṣeba

1 NIGBATI ayaba Ṣeba si gbọ́ okiki Solomoni niti orukọ Oluwa, o wá lati fi àlọ dán a wò. 2 O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀. 3 Solomoni si fi èsi si gbogbo ọ̀rọ rẹ̀, kò si ibère kan ti o pamọ fun ọba ti kò si sọ fun u. 4 Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri gbogbo ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́. 5 Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rẹ̀, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ. 6 O si wi fun ọba pe, Otitọ li ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ ati niti ọgbọ́n rẹ. 7 Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ na gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idajì wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọ́n ati irọra kún okiki ti mo gbọ́. 8 Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro niwaju rẹ nigbagbogbo, ti ngbọ́ ọgbọ́n rẹ. 9 Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o ni inu-didùn si ọ lati gbe ọ ka ori itẹ́ Israeli: nitoriti Oluwa fẹràn Israeli titi lai, nitorina li o ṣe fi ọ jọba, lati ṣe idajọ ati otitọ. 10 On si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọ́pọlọpọ ati okuta iyebiye: iru ọ̀pọlọpọ turari bẹ̃ kò de mọ bi eyiti ayaba Ṣeba fi fun Solomoni, ọba. 11 Pẹlupẹlu awọn ọ̀wọ-ọkọ̀ Hiramu ti o mu wura lati Ofiri wá, mu igi Algumu, (igi Sandali) lọpọlọpọ ati okuta oniyebiye lati Ofiri wá. 12 Ọba si fi igi Algumu na ṣe opó fun ile Oluwa, ati fun ile ọba dùru pẹlu ati ohun-elo orin miran fun awọn akọrin: iru igi Algumu bẹ̃ kò de mọ, bẹ̃ni a kò ri wọn titi di oni yi. 13 Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

Ọrọ̀ Solomoni Ọba

14 Njẹ ìwọn wura ti o nde ọdọ Solomoni li ọdun kan, jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura, 15 Laika eyi ti o ngbà lọwọ awọn ajẹlẹ ati awọn oniṣowo, ati ti gbogbo awọn ọba Arabia, ati ti awọn bãlẹ ilẹ. 16 Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: ẹgbẹta ṣekeli wura li o tán si asà kan. 17 O si ṣe ọdunrun apata wura lilù, oṣuwọn wura mẹta li o tán si apata kan: ọba si ko wọn si ile igbo Lebanoni. 18 Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin kan nla, o si fi wura didara julọ bò o. 19 Itẹ́ na ni atẹgùn mẹfa, oke itẹ́ na yi okiribiti lẹhin: irọpá si wà niha kini ati ekeji ni ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba na. 20 Kiniun mejila duro nibẹ niha ekini ati ekeji lori atẹgùn mẹfa na: a kò ṣe iru rẹ̀ ni ijọba kan. 21 Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni jẹ wura daradara; kò si fadaka; a kò kà a si nkankan li ọjọ Solomoni. 22 Nitori ọba ni ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹlu ọkọ̀ Hiramu li okun: ẹ̃kan li ọdun mẹta li ọkọ̀ Tarṣiṣi idé, ti imu wura ati fadaka, ehin-erin ati inakí ati ẹiyẹ-ologe wá. 23 Solomoni ọba si pọ̀ jù gbogbo awọn ọba aiye lọ, li ọrọ̀ ati li ọgbọ́n. 24 Gbogbo aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀, ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn. 25 Olukuluku nwọn si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadaka, ati ohun-elo wura, ati ẹ̀wu, ati turari, ẹṣin ati ibãka, iye kan lọdọdun. 26 Solomoni si ko kẹkẹ́ ati èṣin jọ: o si ni egbeje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹsin, o si fi wọn si ilu kẹkẹ́, ati pẹlu ọba ni Jerusalemu. 27 Ọba si ṣe ki fadakà ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti mbẹ ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ. 28 A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti li ọwọ́wọ, oniṣowo ọba nmu wọn wá fun owo. 29 Kẹkẹ́ kan ngoke o si njade lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu wá pẹlu nipa ọwọ wọn fun gbogbo awọn ọba awọn ọmọ Hiti ati fun awọn ọba Siria.

1 Ọba 11

Solomoni Yipada Kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun

1 ṢUGBỌN Solomoni ọba fẹràn ọ̀pọ ajeji obinrin, pẹlu ọmọbinrin Farao, awọn obinrin ara Moabu, ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni ati ti awọn ọmọ Hitti. 2 Awọn orilẹ-ède ti Oluwa wi fun awọn ọmọ-Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ wọle tọ̀ wọn, bẹ̃ni awọn kò gbọdọ wọle tọ̀ nyin: nitõtọ nwọn o yi nyin li ọkàn pada si oriṣa wọn: Solomoni fà mọ awọn wọnyi ni ifẹ. 3 O si ni ẽdẹgbẹrin obinrin, awọn ọmọ ọba, ati ọ̃dunrun alè, awọn aya rẹ̀ si yi i li ọkàn pada. 4 O si ṣe, nigbati Solomoni di arugbo, awọn obinrin rẹ̀ yi i li ọkàn pada si ọlọrun miran: ọkàn rẹ̀ kò si ṣe dede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rẹ̀. 5 Nitori Solomoni tọ Aṣtoreti lẹhin, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Milkomu, irira awọn ọmọ Ammoni. 6 Solomoni si ṣe buburu niwaju Oluwa, kò si tọ̀ Oluwa lẹhin ni pipé gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀. 7 Nigbana ni Solomoni kọ́ ibi giga kan fun Kemoṣi, irira Moabu, lori oke ti mbẹ niwaju Jerusalemu, ati fun Moleki, irira awọn ọmọ Ammoni. 8 Bẹ̃li o si ṣe fun gbogbo awọn ajeji obinrin rẹ̀, awọn ti nsun turari, ti nwọn si nrubọ fun oriṣa wọn. 9 Oluwa si binu si Solomoni, nitori ọkàn rẹ̀ yipada kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ara hàn a lẹrinmeji. 10 Ti o si paṣẹ fun u nitori nkan yi pe, Ki o má ṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin: ṣugbọn kò pa eyiti Oluwa fi aṣẹ fun u mọ́. 11 Nitorina Oluwa wi fun Solomoni pe, Nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si pa majẹmu mi, ati aṣẹ mi mọ́, ti mo ti pa laṣẹ fun ọ, ni yiya emi o fà ijọba rẹ ya kuro lọwọ rẹ, emi o si fi i fun iranṣẹ rẹ. 12 Ṣugbọn emi ki yio ṣe e li ọjọ rẹ, nitori Dafidi baba rẹ; emi o fà a ya kuro lọwọ ọmọ rẹ. 13 Kiki pe emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rẹ, nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu ti mo ti yàn.

Àwọn Ọ̀tá Solomoni

14 Oluwa si gbe ọta kan dide si Solomoni, Hadadi, ara Edomu: iru-ọmọ ọba li on iṣe ni Edomu. 15 O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu. 16 Nitori oṣù mẹfa ni Joabu fi joko nibẹ ati gbogbo Israeli, titi o fi ké gbogbo ọkunrin kuro ni Edomu: 17 Hadadi si sá, on ati awọn ara Edomu ninu awọn iranṣẹ baba rẹ̀ pẹlu rẹ̀, lati lọ si Egipti; ṣugbọn Hadadi wà li ọmọde. 18 Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ. 19 Hadadi si ri oju-rere pupọ̀ niwaju Farao, o si fun u li arabinrin aya rẹ̀, li aya, arabinrin Tapenesi, ayaba. 20 Arabinrin Tapenesi si bi Genubati ọmọ rẹ̀ fun u, Tapenesi si já a li ẹnu ọmu ni ile Farao: Genubati si wà ni ile Farao lãrin awọn ọmọ Farao, 21 Nigbati Hadadi si gbọ́ ni Egipti pe, Dafidi sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ati pe Joabu olori-ogun si kú, Hadadi si wi fun Farao pe, rán mi lọ, ki emi ki o le lọ si ilu mi. 22 Nigbana ni Farao wi fun u pe, ṣugbọn kini iwọ ṣe alaini lọdọ mi, si kiyesi i, iwọ nwá ọ̀na lati lọ si ilu rẹ? O si wipe: Kò si nkan: ṣugbọn sa jẹ ki emi ki o lọ. 23 Pẹlupẹlu Ọlọrun gbe ọta dide si i; ani Resoni, ọmọ Eliada, ti o ti sá kuro lọdọ Hadadeseri oluwa rẹ̀, ọba Soba: 24 On si ko enia jọ sọdọ ara rẹ̀, o si di olori-ogun ẹgbẹ́ kan, nigbati Dafidi fi pa wọn, nwọn si lọ si Damasku, nwọn ngbe ibẹ, nwọn si jọba ni Damasku. 25 On si ṣe ọta si Israeli ni gbogbo ọjọ Solomoni, lẹhin ibi ti Hadadi ṣe: Resoni si korira Israeli, o si jọba lori Siria.

Ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Jeroboamu

26 Ati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ara Efrati ti Sereda, iranṣẹ Solomoni, orukọ iya ẹniti ijẹ Serua, obinrin opó kan, on pẹlu gbe ọwọ soke si ọba. 27 Eyi si ni idi ohun ti o ṣe gbe ọwọ soke si ọba: Solomoni kọ́ Millo, o si di ẹya ilu Dafidi baba rẹ̀. 28 Ọkunrin na, Jeroboamu, ṣe alagbara akọni: nigbati Solomoni si ri ọdọmọkunrin na pe, oṣiṣẹ enia ni, o fi i ṣe olori gbogbo iṣẹ-iru ile Josefu. 29 O si ṣe li àkoko na, nigbati Jeroboamu jade kuro ni Jerusalemu, woli Ahijah ara Ṣilo ri i loju ọ̀na; o si wọ̀ agbáda titun; awọn meji pere li o si mbẹ ni oko: 30 Ahijah si gbà agbáda titun na ti o wà lara rẹ̀, o si fà a ya si ọ̀na mejila: 31 O si wi fun Jeroboamu pe, Iwọ mu ẹya mẹwa: nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o fa ijọba na ya kuro li ọwọ Solomoni, emi o si fi ẹya mẹwa fun ọ. 32 Ṣugbọn on o ni ẹya kan nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli: 33 Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀. 34 Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́: 35 Ṣugbọn emi o gba ijọba na li ọwọ ọmọ rẹ̀, emi o si fi i fun ọ, ani ẹya mẹwa. 36 Emi o si fi ẹya kan fun ọmọ rẹ̀, ki Dafidi iranṣẹ mi ki o le ni imọlẹ niwaju mi nigbagbogbo, ni Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn fun ara mi lati fi orukọ mi sibẹ. 37 Emi o si mu ọ, iwọ o si jọba gẹgẹ bi gbogbo eyiti ọkàn rẹ nfẹ, iwọ o si jẹ ọba lori Israeli. 38 Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mã rin li ọ̀na mi, ti iwọ o si mã ṣe eyiti o tọ́ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ́ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ́ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ. 39 Emi o si pọ́n iru-ọmọ Dafidi loju nitori eyi, ṣugbọn kì iṣe titi lai. 40 Nitorina Solomoni wá ọ̀na lati pa Jeroboamu. Jeroboamu si dide, o si sá lọ si Egipti si ọdọ Ṣiṣaki ọba Egipti, o si wà ni Egipti titi ikú Solomoni.

Ikú Solomoni

41 Ati iyokù iṣe Solomoni ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe iṣe Solomoni bi? 42 Ọjọ ti Solomoni jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli jẹ ogoji ọdun. 43 Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

1 Ọba 12

Àwọn ẹ̀yà apá ìhà àríwá dìtẹ̀, wọ́n sì ya

1 REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu, nitori gbogbo Israeli li o wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba. 2 O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o wà ni Egipti sibẹ gbọ́, nitori ti o ti sá kuro niwaju Solomoni ọba, Jeroboamu si joko ni Egipti. 3 Nwọn si ranṣẹ pè e, ati Jeroboamu ati gbogbo ijọ Israeli wá, nwọn si sọ fun Rehoboamu wipe, 4 Baba rẹ sọ àjaga wa di wuwo: njẹ nitorina, ṣe ki ìsin baba rẹ ti o le, ati àjaga rẹ̀ ti o wuwo, ti o fi si wa li ọrùn, ki o fẹrẹ̀ diẹ, awa o si sìn ọ. 5 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ na titi di ijọ mẹta, nigbana ni ki ẹ pada tọ̀ mi wá. Awọn enia na si lọ. 6 Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba, ti imã duro niwaju Solomoni, baba rẹ̀, nigbati o wà lãye, gbimọ̀ wipe, Imọran kili ẹnyin dá, ki emi ki o lè da awọn enia yi lohùn? 7 Nwọn si wi fun u pe, Bi iwọ o ba jẹ iranṣẹ fun awọn enia yi loni, ti iwọ o si sin wọn, ti iwọ o si da wọn lohùn, ati ti iwọ o sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ṣe iranṣẹ rẹ titi lai. 8 Ṣugbọn o kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti nwọn dagba pẹlu rẹ̀, ti nwọn si duro niwaju rẹ̀ gbimọ̀. 9 O si wi fun wọn pe, Imọran kini ẹnyin dá ki awa ki o le dá awọn enia yi lohùn, ti nwọn ba mi sọ wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi si wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ? 10 Awọn ipẹrẹ ti o dagba pẹlu rẹ̀ wi fun u pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn enia yi ti nwọn ba ọ sọ wipe, Baba rẹ mu ki àjaga wa di wuwo, sugbọn iwọ mu ki o fuyẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o sọ fun wọn: ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ. 11 Njẹ nisisiyi, baba mi ti gbe àjaga wuwo kà nyin, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi ti fi paṣan nà nyin, sugbọn emi o fi akẽke nà nyin. 12 Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo awọn enia na wá sọdọ Rehoboamu ni ijọ kẹta, gẹgẹ bi ọba ti dá wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta. 13 Ọba si da awọn enia li ohùn akọ, o si kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá. 14 O si sọ fun wọn gẹgẹ bi ìmọran awọn ipẹrẹ wipe, Baba mi mu ki àjaga nyin ki o wuwo, emi o si bù kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin, 15 Ọba kò si fi eti si ti awọn enia na; nitoriti ọ̀ran na ati ọwọ Oluwa wá ni, ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti Oluwa ti ọwọ Ahijah, ara Ṣilo, sọ fun Jeroboamu, ọmọ Nebati. 16 Bẹ̃ni nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kò fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba li ohùn wipe: Ipin kini awa ni ninu Dafidi? bẹ̃ni awa kò ni iní ninu ọmọ Jesse: Israeli, ẹ pada si agọ nyin: njẹ mã bojuto ile rẹ, Dafidi! Bẹ̃ni Israeli pada sinu agọ wọn. 17 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe inu ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn. 18 Nigbana ni Rehoboamu ọba, ran Adoramu ẹniti iṣe olori iṣẹ-iru; gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Nitorina Rehoboamu, ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀, lati sá lọ si Jerusalemu. 19 Bẹ̃ni Israeli ṣọtẹ̀ si ile Dafidi titi di oni yi. 20 O si ṣe nigbati gbogbo Israeli gbọ́ pe Jeroboamu tun pada bọ̀, ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pè e wá si ajọ, nwọn si fi i jọba lori gbogbo Israeli: kò si ẹnikan ti o tọ̀ ile Dafidi lẹhin, bikoṣe kiki ẹya Juda.

Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya

21 Nigbati Rehoboamu si wá si Jerusalemu, o ko gbogbo ile Juda jọ, pẹlu ẹya Benjamini, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba ile Israeli ja, lati mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu, ọmọ Solomoni. 22 Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Ṣemaiah, enia Ọlọrun wá wipe, 23 Sọ fun Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo ile Juda ati Benjamini, ati fun iyokù awọn enia wipe, 24 Bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò gbọdọ goke bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ẹ pada olukuluku si ile rẹ̀; nitori nkan yi ati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, nwọn si pada lati lọ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

Jeroboamu yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun

25 Nigbana ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu li oke Efraimu o si ngbe inu rẹ̀; o si jade lati ibẹ lọ, o si kọ́ Penueli. 26 Jeroboamu si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Nisisiyi ni ijọba na yio pada si ile Dafidi: 27 Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati ṣe irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalemu, nigbana li ọkàn awọn enia yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mi, nwọn o si tun pada tọ̀ Rehoboamu, ọba Juda lọ. 28 Ọba si gbìmọ, o si ya ẹgbọ̀rọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, O pọ̀ju fun nyin lati mã goke lọ si Jerusalemu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá! 29 O si gbe ọkan kalẹ ni Beteli, ati ekeji li o fi si Dani. 30 Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ: nitori ti awọn enia lọ lati sìn niwaju ọkan, ani titi de Dani. 31 O si kọ́ ile ibi giga wọnni, o si ṣe alufa lati inu awọn enia, ti kì iṣe inu awọn ọmọ Lefi.

Ọlọrun Lòdì sí Ìsìn Bẹtẹli

32 Jeroboamu si dá àse silẹ li oṣu kẹjọ, li ọjọ Kẹdogun oṣu, gẹgẹ bi àse ti o wà ni Juda, o si gun ori pẹpẹ na lọ: bẹ̃ni o si ṣe ni Beteli, o rubọ si awọn ọmọ-malu ti o ṣe: o si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti o ti ṣe si Beteli. 33 O si gun ori pẹpẹ na lọ ti o ti ṣe ni Beteli li ọjọ kẹdogun oṣu kẹjọ, li oṣu ti o rò li ọkàn ara rẹ̀; o si da àse silẹ fun awọn ọmọ Israeli; o si gun ori pẹpẹ na lọ, lati fi turari jona.

1 Ọba 13

1 SI kiyesi i, enia Ọlọrun kan lati Juda wá si Beteli nipa ọ̀rọ Oluwa: Jeroboamu duro lẹba pẹpẹ lati fi turari jona. 2 O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ. 3 O si fun wọn li àmi kan li ọjọ kanna wipe, Eyi li àmi ti Oluwa ti ṣe; Kiyesi i, pẹpẹ na yio ya, ẽru ti mbẹ lori rẹ̀ yio si danu. 4 O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọba gbọ́ ọ̀rọ enia Ọlọrun, ti o ti kigbe si pẹpẹ na, o wipe, Ẹ mu u. Ọwọ́ rẹ̀ ti o nà si i, si gbẹ, bẹ̃ni kò si le fa a pada sọdọ rẹ̀ mọ. 5 Pẹpẹ na si ya, ẽru na si danù kuro ninu pẹpẹ na, gẹgẹ bi àmi ti enia Ọlọrun ti fi fun u nipa ọ̀rọ Oluwa. 6 Ọba si dahùn, o si wi fun enia Ọlọrun na pe, Tù Oluwa Ọlọrun rẹ loju nisisiyi, ki o si gbadura fun mi, ki a ba le tun mu ọwọ́ mi bọ̀ sipo fun mi. Enia Ọlọrun na si tù Ọlọrun loju, a si tun mu ọwọ́ ọba bọ̀ sipo fun u, o si dàbi o ti wà ri. 7 Ọba si wi fun enia Ọlọrun na pe, Wá ba mi lọ ile, ki o si tù ara rẹ lara, emi o si ta ọ li ọrẹ. 8 Enia Ọlọrun na si wi fun ọba pe, Bi iwọ o ba fun mi ni idaji ile rẹ, emi kì yio ba ọ lọ ile, emi kì yio si jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kì yio si mu omi nihin yi. 9 Nitori bẹ̃ li a pa a laṣẹ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Máṣe jẹ onjẹ, má si ṣe mu omi, bẹ̃ni ki o má si ṣe pada li ọ̀na kanna ti o ba wá. 10 Bẹ̃ li o si ba ọ̀na miran lọ, kò si pada li ọ̀na na ti o gbà wá si Beteli.

Wolii Àgbàlagbà Kan, Ará Bẹtẹli

11 Woli àgba kan si ngbe Beteli: ọmọ rẹ̀ de, o si rohin gbogbo iṣẹ ti enia Ọlọrun na ti ṣe li ọjọ na ni Beteli fun u: ọ̀rọ ti o sọ fun ọba nwọn si sọ fun baba wọn. 12 Baba wọn si wi fun wọn pe, Ọna wo li o gbà? Nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti ri ọ̀na ti enia Ọlọrun na gbà, ti o ti Juda wá. 13 O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u o si gùn u. 14 O si tẹ̀le enia Ọlọrun na lẹhin, o si ri i, o joko labẹ igi nla kan: o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun na ti o ti Juda wá? On si wipe, Emi ni. 15 O si wi fun u pe, Ba mi lọ ile, ki o si jẹ onjẹ. 16 On si wipe, Emi kò lè pada lọ pẹlu rẹ, bẹ̃ni emi kò lè ba ọ lọ: bẹ̃ni emi kì o jẹ onjẹ, emi kì o si mu omi pẹlu rẹ nihin yi. 17 Nitori ti a sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Iwọ kò gbọdọ jẹ onjẹ, iwọ kò si gbọdọ mu omi nibẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tun pada lọ nipa ọ̀na ti iwọ ba wá. 18 O si wi fun u pe, Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angeli si sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi. Ṣugbọn o purọ fun u. 19 Bẹ̃ li o si ba a pada lọ, o si jẹ onjẹ ni ile rẹ̀, o si mu omi. 20 O si ṣe, bi nwọn ti joko ti tabili, li ọ̀rọ Oluwa tọ woli na wá ti o mu u padà bọ̀: 21 O si kigbe si enia Ọlọrun ti o ti Juda wá wipe, bayi li Oluwa wi: Niwọn bi iwọ ti ṣe aigbọran si ẹnu Oluwa, ti iwọ kò si pa aṣẹ na mọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ pa fun ọ. 22 Ṣugbọn iwọ pada, iwọ si ti jẹ onjẹ, iwọ si ti mu omi ni ibi ti Oluwa sọ fun ọ pe, Máṣe jẹ onjẹ, ki o má si ṣe mu omi; okú rẹ kì yio wá sinu iboji awọn baba rẹ. 23 O si ṣe, lẹhin igbati o ti jẹ onjẹ, ati lẹhin igbati o ti mu, li o di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u, eyini ni, fun woli ti o ti mu pada bọ̀. 24 Nigbati o si lọ tan, kiniun kan pade rẹ̀ li ọ̀na, o si pa a: a si gbe okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, kẹtẹkẹtẹ si duro tì i, kiniun pẹlu duro tì okú na. 25 Si kiyesi i, awọn enia nkọja, nwọn ri pe, a gbe okú na sọ si oju ọ̀na, kiniun na si duro tì okú na: nwọn si wá, nwọn si sọ ọ ni ilu ti woli àgba na ngbe. 26 Nigbati woli ti o mu u lati ọ̀na pada bọ̀ gbọ́, o wipe, Enia Ọlọrun na ni, ti o ṣọ̀tẹ si Oluwa: nitorina li Oluwa fi i le kiniun lọwọ, ti o si fà a ya, ti o si pa a, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ fun u. 27 O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di i ni gari. 28 O si lọ, o si ri, a gbé okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, ati kẹtẹkẹtẹ, ati kiniun duro ti okú na, kiniun kò jẹ okú na, bẹ̃ni kò fà kẹtẹkẹtẹ na ya. 29 Woli na mu okú enia Ọlọrun na, o si gbé e lori kẹtẹkẹtẹ na, o si mu u pada bọ̀: woli àgba na si wá si ilu, lati ṣọ̀fọ, ati lati sin i. 30 O si tẹ okú rẹ̀ sinu iboji ara rẹ̀: nwọn si sọ̀fọ lori rẹ̀, pe: O ṣe, arakunrin mi! 31 O si ṣe, lẹhin igbati o ti sinkú rẹ̀ tan, o si sọ fun awọn ọmọ rẹ̀ wipe, Nigbati mo ba kú, nigbana ni ki ẹ sinkú mi ni iboji ninu eyiti a sin enia Ọlọrun; ẹ tẹ́ egungun mi lẹba egungun rẹ̀: 32 Nitori ni ṣiṣẹ, ọ̀rọ ti o kigbe nipa ọ̀rọ Oluwa si pẹpẹ na ni Beteli, ati si gbogbo ile ibi giga ti mbẹ ni gbogbo ilu Samaria, yio ṣẹ dandan.

Ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣe ikú pa Jeroboamu

33 Lẹhin nkan yi, Jeroboamu kò pada kuro ninu ọ̀na ibi rẹ̀, ṣugbọn o tun mu ninu awọn enia ṣe alufa ibi giga wọnni: ẹnikẹni ti o ba fẹ, a yà a sọtọ̀ on a si di alufa ibi giga wọnni. 34 Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ani lati ke e kuro, ati lati pa a run kuro lori ilẹ.

1 Ọba 14

Ikú ọmọ Jeroboamu ọkunrin

1 Li àkoko na, Abijah ọmọ Jeroboamu ṣàisan. 2 Jeroboamu si wi fun aya rẹ̀ pe, Dide, emi bẹ̀ ọ, si pa ara rẹ dà, ki a má ba le mọ̀ ọ li aya Jeroboamu; ki o si lọ si Ṣilo: kiyesi i, nibẹ li Ahijah, woli wà, ti o sọ fun mi pe, emi o jọba lori enia yi. 3 Ki o si mu ìṣu àkara mẹwa li ọwọ́ rẹ, ati akara wẹwẹ, ati igo oyin, ki o si lọ sọdọ rẹ̀: on o si wi fun ọ bi yio ti ri fun ọmọde na. 4 Aya Jeroboamu si ṣe bẹ̃, o si dide, o si lọ si Ṣilo, o si wá si ile Ahijah. Ṣugbọn Ahijah kò riran; nitoriti oju rẹ̀ fọ́ nitori ogbó rẹ̀. 5 Oluwa si wi fun Ahijah, pe, Kiyesi i, aya Jeroboamu mbọ̀ wá bère ohun kan lọwọ rẹ niti ọmọ rẹ̀: nitori ti o ṣàisan: bayi bayi ni ki iwọ ki o wi fun u: yio si ṣe, nigbati o ba wọle, yio ṣe ara rẹ̀ bi ẹlomiran. 6 Bẹ̃ li o si ri, nigbati Ahijah gbọ́ iró ẹsẹ rẹ̀, bi o ti mbọ̀ wá li ẹnu ọ̀na, on si wipe, Wọle wá, iwọ, aya Jeroboamu, ẽṣe ti iwọ fi ṣe ara rẹ bi ẹlomiran? nitori iṣẹ wuwo li a fi rán mi si ọ. 7 Lọ, sọ fun Jeroboamu, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Nitori bi mo ti gbé ọ ga lati inu awọn enia, ti mo si fi ọ jẹ olori Israeli enia mi. 8 Ti mo si fà ijọba ya kuro ni ile Dafidi, mo si fi i fun ọ: sibẹ iwọ kò ri bi Dafidi iranṣẹ mi, ẹniti o pa ofin mi mọ, ti o si tọ̀ mi lẹhin tọkàntọkàn rẹ̀, lati ṣe kiki eyi ti o tọ li oju mi: 9 Ṣugbọn iwọ ti ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o ti wà ṣaju rẹ: nitori iwọ ti lọ, iwọ si ti ṣe awọn ọlọrun miran, ati ere didà, lati ru ibinu mi, ti iwọ si ti gbé mi sọ si ẹhin rẹ: 10 Nitorina, kiyesi i, emi o mu ibi wá si ile Jeroboamu, emi o ke gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Jeroboamu, ati ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli, emi o si mu awọn ti o kù ni ile Jeroboamu kuro, gẹgẹ bi enia ti ikó igbẹ kuro, titi gbogbo rẹ̀ yio fi tan. 11 Ẹni Jeroboamu ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ: ati ẹniti o ba kú ni igbẹ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio jẹ: nitori Oluwa ti sọ ọ. 12 Nitorina, iwọ dide, lọ si ile rẹ: nigbati ẹsẹ rẹ ba si wọ̀ ilu, ọmọ na yio kú. 13 Gbogbo Israeli yio si ṣọ̀fọ rẹ̀, nwọn o si sin i; nitori kiki on nikan li ẹniti yio wá si isa-okú ninu ẹniti iṣe ti Jeroboamu, nitori lọdọ rẹ̀ li a ri ohun rere diẹ sipa Oluwa, Ọlọrun Israeli, ni ile Jeroboamu. 14 Oluwa yio si gbé ọba kan dide lori Israeli, ti yio ke ile Jeroboamu kuro li ọjọ na: ṣugbọn kini? ani nisisiyi! 15 Nitoriti Oluwa yio kọlu Israeli bi a ti imì iye ninu omi, yio si fa Israeli tu kuro ni ilẹ rere yi, ti o ti fi fun awọn baba wọn, yio si fọ́n wọn ka kọja odò na, nitoriti nwọn ṣe ere oriṣa wọn, nwọn si nru ibinu Oluwa. 16 Yio si kọ̀ Israeli silẹ nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ẹniti o ṣẹ̀, ti o si mu Israeli dẹṣẹ. 17 Aya Jeroboamu si dide, o si lọ, o si de Tira: nigbati o si wọ̀ iloro ile, ọmọde na si kú; 18 Nwọn si sin i; gbogbo Israeli si sọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah woli.

Ikú Jeroboamu

19 Ati iyokù iṣe Jeroboamu, bi o ti jagun, ati bi o ti jọba, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. 20 Awọn ọjọ ti Jeroboamu jọba jẹ ọdun mejilelogun, o si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Rehoboamu, Ọba Juda

21 Rehoboamu, ọmọ Solomoni, si jọba ni Juda: Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanlelogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. 22 Juda si ṣe buburu niwaju Oluwa, nwọn si fi ẹ̀ṣẹ wọn mu u jowu jù gbogbo eyiti baba wọn ti ṣe, ti nwọn si ti dá. 23 Nitori awọn pẹlu kọ́ ibi giga fun ara wọn, ati ere, ati igbo-oriṣa lori gbogbo oke giga, ati labẹ gbogbo igi tutu. 24 Awọn ti nhùwa panṣaga mbẹ ni ilẹ na: nwọn si ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun irira awọn orilẹ-ède ti Oluwa lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli. 25 O si ṣe li ọdun karun Rehoboamu ọba, Ṣiṣaki, ọba Egipti goke wá si Jerusalemu: 26 O si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; ani gbogbo rẹ̀ li o kó lọ: o si kó gbogbo asà wura ti Solomoni ti ṣe lọ. 27 Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn si ọwọ́ olori awọn oluṣọ ti nṣọ ilẹkun ile ọba. 28 Bẹ̃li o si ri, nigbati ọba ba nlọ si ile Oluwa, nwọn a rù wọn, nwọn a si mu wọn pada sinu yara oluṣọ. 29 Iyokù iṣe Rehoboamu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 30 Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ wọn gbogbo. 31 Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. Abijah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

1 Ọba 15

Abijamu, Ọba Juda

1 NJẸ li ọdun kejidilogun Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, Abijah jọba lori Juda. 2 Ọdun mẹta li o jọba ni Jerusalemu: orukọ iya rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. 3 O si rin ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀, ti o ti dá niwaju rẹ̀: ọkàn rẹ̀ kò si pé pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọkàn Dafidi baba rẹ̀. 4 Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ: 5 Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti. 6 Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. 7 Njẹ iyokù iṣe Abijah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu. 8 Abijah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sin i ni ilu Dafidi: Asa, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Aṣa, Ọba Juda

9 Ati li ogun ọdun Jeroboamu ọba Israeli, ni Asa jọba lori Juda. 10 Ọdun mọkanlelogoji li o jọba ni Jerusalemu, orukọ iya nla rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. 11 Asa si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, bi Dafidi baba rẹ̀. 12 O si mu awọn ti nṣe panṣaga kuro ni ilẹ na, o si kó gbogbo ere ti awọn baba rẹ̀ ti ṣe kuro. 13 Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni. 14 Ṣugbọn ibi giga wọnnì ni a kò mu kuro; sibẹ ọkàn Asa pé pẹlu Oluwa li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. 15 O si mu ohun-mimọ́ wọnnì ti baba rẹ̀, ati ohun-mimọ́ wọnnì ti on tikararẹ̀ wọ ile Oluwa, fadaka ati wura, ati ohun-elo wọnnì, 16 Ogun si wà lãrin Asa ati Baaṣa, ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn. 17 Baaṣa, ọba Israeli, si goke lọ si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má le jẹ ki ẹnikẹni ki o jade tabi ki o wọle tọ Asa ọba lọ. 18 Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe, 19 Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi. 20 Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali. 21 O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o si ṣiwọ ati kọ́ Rama, o si ngbe Tirsa. 22 Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa. 23 Iyokù gbogbo iṣe Asa, ati gbogbo agbara rẹ̀ ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati ilu wọnnì ti o kọ́, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ṣugbọn li akoko ogbó rẹ̀, àrun ṣe e li ẹsẹ rẹ̀. 24 Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Nadabu, Ọba Israẹli

25 Nadabu ọmọ Jeroboamu si bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli li ọdun keji Asa, ọba Juda, o si jọba lori Israeli li ọdun meji. 26 O si ṣe buburu niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ eyiti o mu Israeli ṣẹ̀. 27 Baaṣa ọmọ Ahijah ti ile Issakari, si dìtẹ si i; Baaṣa kọlu u ni Gibbetoni ti awọn ara Filistia: nitori Nadabu ati gbogbo Israeli dó ti Gibbetoni. 28 Ani li ọdun kẹta ti Asa ọba Juda, ni Baaṣa pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀. 29 O si ṣe, nigbati o jọba, o kọlu gbogbo ile Jeroboamu; kò kù fun Jeroboamu ẹniti nmí, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Ọluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah ara Ṣilo: 30 Nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀, ti o si mu ki Israeli ṣẹ̀, nipa imunibinu rẹ̀, eyiti o fi mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli ki o binu. 31 Ati iyokù iṣe Nadabu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. 32 Ogun si wà, lãrin Asa ati Baaṣa ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn.

Baaṣa, Ọba Israẹli

33 Li ọdun kẹta Asa, ọba Juda, ni Baaṣa, ọmọ Ahijah bẹ̀rẹ si ijọba lori gbogbo Israeli ni Tirsa, li ọdun mẹrinlelogun. 34 O si ṣe buburu niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na Jeroboamu, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀.

1 Ọba 16

1 O si ṣe, ọ̀rọ Oluwa tọ Jehu, ọmọ Hanani wá, si Baaṣa wipe, 2 Bi o ti ṣepe mo gbé ọ ga lati inu ẽkuru wá, ti mo si ṣe ọ li olori Israeli, enia mi; iwọ si rìn li ọ̀na Jeroboamu, iwọ si ti mu ki Israeli enia mi ki o ṣẹ̀, lati fi ẹ̀ṣẹ wọn mu mi binu; 3 Kiyesi i, emi o mu iran Baaṣa, ati iran ile rẹ̀ kuro; emi o si ṣe ile rẹ̀ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati. 4 Ẹni Baaṣa ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ; ati ẹni rẹ̀ ti o kú ni oko li ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ. 5 Ati iyokù iṣe Baaṣa, ati ohun ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. 6 Baaṣa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Tirsa: Ela, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀. 7 Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a.

Ela, Ọba Israẹli

8 Li ọdun kẹrindilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Tirsa li ọdun meji. 9 Ati iranṣẹ rẹ̀ Simri, olori idaji kẹkẹ́ rẹ̀, dìtẹ rẹ̀, nigbati o ti wà ni Tirsa, o si mu amupara ni ile Arsa, iriju ile rẹ̀ ni Tirsa. 10 Simri si wọle o si kọlù u, o si pa a, li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, o si jọba ni ipò rẹ̀. 11 O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀. 12 Bayi ni Simri pa gbogbo ile Baaṣa run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ si Baaṣa nipa ọwọ́ Jehu woli, 13 Nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ Baaṣa, ati Ela, ọmọ rẹ̀, nipa eyiti nwọn ṣẹ̀, ati nipa eyiti nwọn mu Israeli ṣẹ̀, ni fifi ohun-asán wọn wọnnì mu ki Oluwa, Ọlọrun Israeli binu. 14 Ati iyokù iṣe Ela, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

Simiri, Ọba Israẹli

15 Li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Simri jọba ijọ meje ni Tirsa. Awọn enia si do tì Gibbetoni, ti awọn ara Filistia. 16 Awọn enia ti o dotì gbọ́ wipe, Simri ditẹ̀ o si ti pa ọba pẹlu: nitorina gbogbo Israeli fi Omri, olori ogun, jẹ ọba lori Israeli li ọjọ na ni ibudo. 17 Omri si goke lati Gibbetoni lọ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, nwọn si do tì Tirsa. 18 O si ṣe, nigbati Simri mọ̀ pe a gba ilu, o wọ inu ãfin ile ọba lọ, o si tẹ iná bọ ile ọba lori ara rẹ̀, o si kú. 19 Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀. 20 Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

Omiri, Ọba Israẹli

21 Nigbana li awọn enia Israeli da meji; apakan awọn enia ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin, lati fi i jọba, apakan si ntọ̀ Omri lẹhin. 22 Ṣugbọn awọn enia ti ntọ̀ Omri lẹhin bori awọn ti ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin: bẹ̃ni Tibni kú, Omri si jọba. 23 Li ọdun kọkanlelọgbọn Asa, ọba Juda, ni Omri bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli fun ọdun mejila: ọdun mẹfa li o jọba ni Tirsa. 24 O si rà oke Samaria lọwọ Semeri ni talenti meji fadaka, o si tẹdo lori oke na, o si pe orukọ ilu na ti o tẹ̀do ni Samaria nipa orukọ Semeri, oluwa oke Samaria. 25 Ṣugbọn Omri ṣe buburu li oju Oluwa, o si ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o wà ṣãju rẹ̀. 26 Nitori ti o rìn ni gbogbo ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀, lati fi ohun-asán wọn wọnni mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu. 27 Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 28 Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ahabu Ọba Israẹli

29 Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun, 30 Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ. 31 O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ, 32 O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria. 33 Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu. 34 Li ọjọ rẹ̀ ni Hieli, ara Beteli, kọ́ Jeriko: o fi ipilẹ rẹ̀ le ilẹ ni Abiramu, akọbi rẹ̀, o si gbé awọn ilẹkun ibode rẹ̀ kọ́ ni Segubu abikẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Joṣua, ọmọ Nuni sọ.

1 Ọba 17

Elija ati Ọ̀dá

1 ELIJAH ara Tiṣbi, lati inu awọn olugbe Gileadi, wi fun Ahabu pe, Bi Oluwa Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọ̀rọ mi. 2 Ọrọ Oluwa si tọ̀ ọ wá wipe: 3 Kuro nihin, ki o si kọju siha ila-õrun, ki o si fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani. 4 Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ. 5 O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani. 6 Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na. 7 O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.

Elija ati Opó kan, ará Sarefati

8 Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe, 9 Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ. 10 On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu. 11 Bi o si ti nlọ bù u wá, o ke si i, o si wipe, Jọ̃, mu okele onjẹ diẹ fun mi wá lọwọ rẹ. 12 On si wipe, Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, emi kò ni àkara, ṣugbọn ikunwọ iyẹfun ninu ìkoko, ati ororo diẹ ninu kòlobo: si kiyesi i, emi nṣa igi meji jọ, ki emi ki o le wọle lọ, ki emi ki o si peṣe rẹ̀ fun mi, ati fun ọmọ mi, ki awa le jẹ ẹ, ki a si kú. 13 Elijah si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; lọ, ki o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi; ṣugbọn ki o tètekọ ṣe àkara kekere kan fun mi ninu rẹ̀ na, ki o si mu u fun mi wá, lẹhin na, ki o ṣe tirẹ ati ti ọmọ rẹ: 14 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: Ikoko iyẹfun na kì yio ṣòfo, bẹni kólobo ororo na kì yio gbẹ, titi di ọjọ ti Oluwa yio rọ̀ òjo si ori ilẹ. 15 O si lọ, o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Elijah: ati on ati obinrin na, ati ile rẹ̀ jẹ li ọjọ pupọ̀. 16 Ikoko iyẹfun na kò ṣòfo, bẹ̃ni kólobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Elijah sọ. 17 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni ọmọ obinrin na, iya ile na, ṣe aisàn; aisàn rẹ̀ na si le to bẹ̃, ti kò kù ẹmi ninu rẹ̀. 18 On si wi fun Elijah pe, Kili o ṣe mi ṣe ọ, Iwọ enia Ọlọrun? iwọ ha tọ̀ mi wá lati mu ẹ̀ṣẹ mi wá si iranti, ati lati pa mi li ọmọ? 19 On si wi fun u pe, Gbé ọmọ rẹ fun mi. Elijah si yọ ọ jade li aiya rẹ̀, o si gbé e lọ si iyara-òke ile nibiti on ngbe, o si tẹ́ ẹ si ori akete tirẹ̀. 20 O si kepe OLUWA, o si wipe, OLUWA Ọlọrun mi, iwọ ha mu ibi wá ba opó na pẹlu lọdọ ẹniti emi nṣe atipo, ni pipa ọmọ rẹ̀? 21 On si nà ara rẹ̀ lori ọmọde na li ẹrinmẹta, o si kepe Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi ọmọde yi ki o tun padà wá sinu rẹ̀. 22 Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji. 23 Elijah si mu ọmọde na, o si mu u sọkalẹ lati inu iyara-òke na wá sinu ile, o si fi i le iya rẹ̀ lọwọ: Elijah si wipe, Wò o, ọmọ rẹ yè. 24 Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ̀ pe, enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe, ọ̀rọ Oluwa li ẹnu rẹ, otitọ ni.

1 Ọba 18

Elija ati Àwọn Wolii Baali

1 O si ṣe, lẹhin ọjọ pupọ, ọ̀rọ Oluwa tọ Elijah wá lọdun kẹta, wipe, Lọ, fi ara rẹ hàn Ahabu; emi o si rọ̀ òjo sori ilẹ. 2 Elijah si lọ ifi ara rẹ̀ han Ahabu. Iyan nla si mu ni Samaria. 3 Ahabu si pe Obadiah, ti iṣe olori ile rẹ̀. Njẹ Obadiah bẹ̀ru Oluwa gidigidi: 4 O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn. 5 Ahabu si wi fun Obadiah pe, Rin ilẹ lọ, si orisun omi gbogbo, ati si odò gbogbo: bọya awa le ri koriko lati gbà awọn ẹṣin ati awọn ibãka là, ki a má ba ṣòfo awọn ẹranko patapata. 6 Nwọn si pin ilẹ na lãrin ara wọn, lati là a ja: Ahabu gba ọ̀na kan lọ fun ara rẹ̀, Obadiah si gba ọ̀na miran lọ fun ara rẹ̀. 7 Nigbati Obadiah si wà li ọ̀na, kiyesi i, Elijah pade rẹ̀: nigbati o mọ̀ ọ, o si doju rẹ̀ bolẹ, o si wipe, Ṣé iwọ oluwa mi Elijah nìyí? 8 O si da a lohùn pe, Emi ni: lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin. 9 On si wipe, Ẹ̀ṣẹ kini mo ha dá, ti iwọ fẹ fi iranṣẹ rẹ le Ahabu lọwọ lati pa mi? 10 Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, kò si orilẹ-ède tabi ijọba kan, nibiti oluwa mi kò ranṣẹ de lati wò ọ: nigbati nwọn ba si wipe, Kò si; on a mu ki ijọba tabi orilẹ-ède na bura pe: awọn kò ri ọ. 11 Nisisiyi iwọ si wipe, Lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin; 12 Yio si ṣe bi emi o ti lọ kuro li ọdọ rẹ, Ẹmi Oluwa yio si gbe ọ lọ si ibi ti emi kò mọ̀; nigbati mo ba si de, ti mo si wi fun Ahabu, ti kò ba si ri ọ, on o pa mi: ṣugbọn emi, iranṣẹ rẹ, bẹ̀ru Oluwa lati igba ewe mi wá. 13 A kò ha sọ fun oluwa mi, ohun ti mo ṣe nigbati Jesebeli pa awọn woli Oluwa, bi mo ti pa ọgọrun enia mọ ninu awọn woli Oluwa li aradọta ninu ihò-okuta, ti mo si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn? 14 Nisisiyi, iwọ si wipe, Lọ sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin! on o si pa mi. 15 Elijah si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, nitõtọ, emi o fi ara mi han fun u loni yi. 16 Bẹ̃ni Obadiah lọ lati pade Ahabu, o si sọ fun u: Ahabu si lọ lati pade Elijah. 17 O si ṣe, bi Ahabu ti ri Elijah, Ahabu si wi fun u pe, Iwọ li ẹniti nyọ Israeli li ẹnu! 18 On sì dahùn pe, Emi kò yọ Israeli li ẹnu; bikoṣe iwọ ati ile baba rẹ, ninu eyiti ẹnyin ti kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ti iwọ si ti ntọ̀ Baalimu lẹhin. 19 Nitorina, ranṣẹ nisisiyi, ki o si kó gbogbo Israeli jọ sọdọ mi si oke Karmeli ati awọn woli Baali ãdọtalenirinwo, ati awọn woli ere-oriṣa irinwo, ti njẹun ni tabili Jesebeli. 20 Bẹ̃ni Ahabu ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si kó awọn woli jọ si oke Karmeli. 21 Elijah si tọ gbogbo awọn enia na wá, o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin! Awọn enia na kò si da a li ohùn ọ̀rọ kan. 22 Elijah si wi fun awọn enia na pe, Emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù ni woli Oluwa; ṣugbọn awọn woli Baali ãdọta-lenirinwo ọkunrin, 23 Nitorina jẹ ki nwọn ki o fun wa li ẹgbọrọ akọ-malu meji; ki nwọn ki o si yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara wọn, ki nwọn ki o si ke e, ki nwọn ki o si tò o si ori igi, ki nwọn ki o má ṣe fi iná si i: emi o si tun ẹgbọrọ akọ-malu keji ṣe, emi o si tò o sori igi, emi kì o si fi iná si i. 24 Ki ẹ si kepe orukọ awọn ọlọrun nyin, emi o si kepè orukọ Oluwa: Ọlọrun na ti o ba fi iná dahùn on na li Ọlọrun. Gbogbo awọn enia na si dahùn, nwọn si wipe, O wi i re. 25 Elijah si wi fun awọn woli Baali pe, Ẹ yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara nyin, ki ẹ si tètekọ ṣe e: nitori ẹnyin pọ̀: ki ẹ si kepè orukọ awọn ọlọrun nyin, ṣugbọn ẹ máṣe fi iná si i, 26 Nwọn si mu ẹgbọrọ akọ-malu na ti a fi fun wọn, nwọn si ṣe e, nwọn si kepè orukọ Baali lati owurọ titi di ọ̀sangangan wipe, Baali! da wa lohùn. Ṣugbọn kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn. Nwọn si jó yi pẹpẹ na ka, eyiti nwọn tẹ́. 27 O si ṣe, li ọ̀sangangan ni Elijah fi wọn ṣe ẹlẹya o si wipe, Ẹ kigbe lohùn rara, ọlọrun sa li on; bọya o nṣe àṣaro, tabi on nlepa, tabi o re àjo, bọya o sùn, o yẹ ki a ji i. 28 Nwọn si kigbe lohùn rara, nwọn si fi ọbẹ ati ọ̀kọ ya ara wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, titi ẹ̀jẹ fi tu jade li ara wọn. 29 O si ṣe, nigbati ọjọ kan atarí, nwọn si nfi were sọtẹlẹ titi di akoko irubọ aṣalẹ, kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn, tabi ẹniti o kà a si. 30 Njẹ Elijah wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹ sunmọ mi. Gbogbo awọn enia na si sunmọ ọ. On si tun pẹpẹ Oluwa ti o ti wo lulẹ ṣe. 31 Elijah si mu okuta mejila, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya ọmọ Jakobu, ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá, wipe, Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ: 32 Okuta wọnyi li o fi tẹ́ pẹpẹ kan li orukọ Oluwa, o si wà kòtò yi pẹpẹ na ka, ti o le gba iwọn oṣùwọn irugbin meji. 33 O si to igi na daradara, o si ke ẹgbọrọ akọ-malu na, o si tò o sori igi, o si wipe, fi omi kún ikoko mẹrin, ki ẹ si tú u sori ẹbọ sisun ati sori igi na. 34 O si wipe, Ṣe e nigba keji. Nwọn si ṣe e nigba keji. O si wipe, Ṣe e nigba kẹta. Nwọn si ṣe e nigba kẹta. 35 Omi na si ṣàn yi pẹpẹ na ka, o si fi omi kún kòtò na pẹlu. 36 O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ. 37 Gbọ́ ti emi, Oluwa, gbọ́ ti emi, ki awọn enia yi ki o le mọ̀ pe, Iwọ Oluwa li Ọlọrun, ati pe, Iwọ tún yi ọkàn wọn pada. 38 Nigbana ni iná Oluwa bọ́ silẹ, o si sun ẹbọsisun na ati igi, ati okuta wọnnì, ati erupẹ o si lá omi ti mbẹ ninu yàra na. 39 Nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn da oju wọn bolẹ: nwọn si wipe, Oluwa, on li Ọlọrun; Oluwa, on li Ọlọrun! 40 Elijah si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn woli Baali; máṣe jẹ ki ọkan ninu wọn ki o salà. Nwọn si mu wọn: Elijah si mu wọn sọkalẹ si odò Kiṣoni, o si pa wọn nibẹ.

Ọ̀dá Parí

41 Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ. 42 Bẹ̃ni Ahabu goke lọ lati jẹ ati lati mu. Elijah si gun ori oke Karmeli lọ; o si tẹriba o si fi oju rẹ̀ si agbedemeji ẽkun rẹ̀, 43 O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje. 44 O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro. 45 O si ṣe, nigba diẹ si i, ọrun si ṣu fun awọsanmọ on iji, òjo pupọ si rọ̀. Ahabu si gun kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli. 46 Ọwọ́ Oluwa si mbẹ lara Elijah: o si di amure ẹ̀gbẹ rẹ̀, o si sare niwaju Ahabu titi de Jesreeli.

1 Ọba 19

Elija, lórí Òkè Sinai

1 AHABU si sọ ohun gbogbo, ti Elijah ti ṣe, fun Jesebeli, ati pẹlu bi o ti fi idà pa gbogbo awọn woli. 2 Nigbana ni Jesebeli rán onṣẹ kan si Elijah, wipe, Bẹ̃ni ki awọn òriṣa ki o ṣe si mi ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi emi kò ba ṣe ẹmi rẹ dabi ọkan ninu wọn ni iwoyi ọla. 3 O si bẹ̀ru, o si dide, o si lọ fun ẹmi rẹ̀, o si de Beerṣeba ti Juda, o si fi ọmọ-ọdọ rẹ̀ silẹ nibẹ. 4 Ṣugbọn on tikararẹ̀ lọ ni irin ọjọ kan si aginju, o si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan, o si tọrọ fun ara rẹ̀ ki on ba le kú; o si wipe, O to; nisisiyi, Oluwa, gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn jù awọn baba mi lọ! 5 Bi o si ti dùbulẹ ti o si sùn labẹ igi juniperi kan, si wò o, angeli fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wi fun u pe, Dide, jẹun. 6 O si wò, si kiyesi i, àkara ti a din lori ẹyin iná, ati orù-omi lẹba ori rẹ̀: o si jẹ, o si mu, o si tun dùbulẹ. 7 Angeli Oluwa si tun pada wá lẹrinkeji, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wipe, Dide, jẹun; nitoriti ọ̀na na jìn fun ọ. 8 O si dide, o si jẹ, o mu, o si lọ li agbara onjẹ yi li ogoji ọsan ati ogoji oru si Horebu, oke Ọlọrun. 9 O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah? 10 On si wipe, Ni jijowu emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ: ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù, nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. 11 O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na. 12 Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere. 13 O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah? 14 On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. 15 Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria. 16 Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ. 17 Yio si ṣe, ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Hasaeli ni Jehu yio pa, ati ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Jehu ni Eliṣa yio pa. 18 Ṣugbọn emi ti kù ẹ̃dẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israeli, gbogbo ẽkun ti kò tii kunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kò iti fi ẹnu kò o li ẹnu.

Ìpè Eliṣa

19 Bẹ̃ni o pada kuro nibẹ, o si ri Eliṣa, ọmọ Ṣafati o nfi àjaga malu mejila tulẹ niwaju rẹ̀, ati on na pẹlu ikejila: Elijah si kọja tọ̀ ọ lọ, o si da agbáda rẹ̀ bò o. 20 O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ? 21 O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u.

1 Ọba 20

Israẹli bá Siria Jagun

1 BENHADADI, oba Siria si gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ: ọba mejilelọgbọn si mbẹ pẹlu rẹ̀ ati ẹṣin ati kẹkẹ́: o si gokè lọ, o si dóti Samaria, o ba a jagun. 2 O si rán awọn onṣẹ sinu ilu, sọdọ Ahabu, ọba Ìsraeli, o si wi fun u pe, Bayi ni Benhadadi wi. 3 Fadaka rẹ ati wura rẹ ti emi ni; awọn aya rẹ pẹlu ati awọn ọmọ rẹ, ani awọn ti o dara jùlọ, temi ni nwọn. 4 Ọba Israeli si dahùn o si wipe, oluwa mi, ọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ tirẹ li emi, ati ohun gbogbo ti mo ni. 5 Awọn onṣẹ si tun padà wá, nwọn si wipe, Bayi ni Benhadadi sọ wipe, Mo tilẹ ranṣẹ si ọ wipe, Ki iwọ ki o fi fadaka rẹ ati wura rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ le mi lọwọ; 6 Nigbati emi ba rán awọn iranṣẹ mi si ọ ni iwòyi ọla, nigbana ni nwọn o wá ile rẹ wò, ati ile awọn iranṣẹ rẹ; yio si ṣe, ohunkohun ti o ba dara loju rẹ, on ni nwọn o fi si ọwọ́ wọn, nwọn o si mu u lọ. 7 Nigbana ni ọba Israeli pè gbogbo awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ fiyèsi i, emi bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò bi ọkunrin yi ti nfẹ́ ẹ̀fẹ: nitoriti o ranṣẹ si mi fun awọn aya mi, ati fun awọn ọmọ mi, ati fun fadaka mi, ati fun wura mi, emi kò si fi dù u. 8 Ati gbogbo awọn àgba ati gbogbo awọn enia wi fun u pe, Máṣe fi eti si tirẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe gbà fun u. 9 Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá. 10 Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi. 11 Ọba Israeli si dahùn, o si wipe, Wi fun u pe, Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ́ ọ silẹ, 12 O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na. 13 Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa. 14 Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ. 15 Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin. 16 Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ. 17 Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá. 18 On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye. 19 Bẹ̃ni awọn ipẹrẹ̀ wọnyi ti awọn ijoye igberiko jade ti ilu wá, ati ogun ti o tẹle wọn. 20 Nwọn si pa, olukuluku ọkunrin kọkan; awọn ara Siria sa; Israeli si lepa wọn: Benhadadi, ọba Siria si sala lori ẹṣin pẹlu awọn ẹlẹṣin. 21 Ọba Israeli si jade lọ, o si kọlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ́, o pa awọn ara Siria li ọ̀pọlọpọ. 22 Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.

Siria Tún Gbógun ti Israẹli Nígbà Keji

23 Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ. 24 Nkan yi ni ki o si ṣe, mu awọn ọba kuro, olukuluku kuro ni ipò rẹ̀, ki o si fi olori-ogun si ipò wọn. 25 Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃. 26 O si ṣe li amọdun, ni Benhadadi kà iye awọn ara Siria, nwọn si goke lọ si Afeki, lati bá Israeli jagun. 27 A si ka iye awọn ọmọ Israeli, nwọn si pese onjẹ, nwọn si lọ ipade wọn: awọn ọmọ Israeli si dó niwaju wọn gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji: ṣugbọn awọn ara Siria kún ilẹ na. 28 Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa. 29 Nwọn si dó, ekini tì ekeji ni ijọ meje. O si ṣe, li ọjọ keje, nwọn padegun, awọn ọmọ Israeli si pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ̀ ninu awọn ara Siria li ọjọ kan. 30 Sugbọn awọn iyokù salọ si Afeki, sinu ilu; odi si wolu ẹgbamẹtala-le-ẹgbẹrun ninu awọn enia ti o kù. Benhadadi si sa lọ, o si wá sinu ilu lati iyẹwu de iyẹwu. 31 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Kiyesi i, nisisiyi, awa ti gbọ́ pe, awọn ọba ile Israeli, alãnu ọba ni nwọn: mo bẹ ọ, jẹ ki awa ki o fi aṣọ-ọ̀fọ si ẹgbẹ wa, ati ijará yi ori wa ka, ki a si jade tọ̀ ọba Israeli lọ: bọya on o gba ẹmi rẹ là. 32 Bẹ̃ni nwọn di aṣọ ọ̀fọ mọ ẹgbẹ wọn, nwọn si fi ijara yi ori wọn ka, nwọn si tọ̀ ọba Israeli wá, nwọn si wipe, Benhadadi, iranṣẹ rẹ, wipe, Emi bẹ ọ, jẹ ki ẹmi mi ki o yè. On si wipe, O mbẹ lãye sibẹ? arakunrin mi li on iṣe. 33 Awọn ọkunrin na si ṣe akiyesi gidigidi, nwọn si yara gbá ohun ti o ti ọdọ rẹ̀ wá mu: nwọn si wipe, Benhadadi arakunrin rẹ! Nigbana li o wipe, Ẹ lọ mu u wá. Nigbana ni Benhadadi jade tọ̀ ọ wá; o si mu u goke wá sinu kẹkẹ́. 34 On si wi fun u pe, Awọn ilu ti baba mi gbà lọwọ baba rẹ, emi o mu wọn pada: iwọ o si là ọ̀na fun ara rẹ ni Damasku, bi baba mi ti ṣe ni Samaria. Nigbana ni Ahabu wipe, Emi o rán ọ lọ pẹlu majẹmu yi. Bẹ̃ li o ba a dá majẹmu, o si rán a lọ.

Wolii kan Dá Ahabu lẹ́bi

35 Ọkunrin kan ninu awọn ọmọ awọn woli si wi fun ẹnikeji rẹ̀ nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si kọ̀ lati lù u. 36 Nigbana li o wi pe, Nitoriti iwọ kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, kiyesi i, bi iwọ ba ti ọdọ mi kuro, kiniun yio pa ọ. Bi o si ti jade lọ lọdọ rẹ̀, kiniun kan ri i o si pa a. 37 Nigbana li o si ri ọkunrin miran, o si wipe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si lù u, ni lilu ti o lù u, o pa a lara. 38 Woli na si lọ, o si duro de ọba loju ọ̀na, o pa ara rẹ̀ da, ni fifi ẽru ba oju. 39 Bi ọba si ti nkọja lọ, o ke si ọba o si wipe, iranṣẹ rẹ jade wọ arin ogun lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan yà sapakan, o si mu ọkunrin kan fun mi wá o si wipe: Pa ọkunrin yi mọ; bi a ba fẹ ẹ kù, nigbana ni ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, bi bẹ̃ kọ, iwọ o san talenti fadaka kan. 40 Bi iranṣẹ rẹ si ti ni iṣe nihin ati lọhun, a fẹ ẹ kù. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃ni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti dá a. 41 O si yara, o si mu ẹ̃ru kuro li oju rẹ̀; ọba Israeli si ri i daju pe, ọkan ninu awọn woli ni on iṣe. 42 O si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ, ọkunrin ti emi ti yàn si iparun patapata, ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, ati enia rẹ fun enia rẹ̀. 43 Ọba Israeli si lọ si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ o si wá si Samaria.

1 Ọba 21

Ọgbà Àjàrà Naboti

1 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, Naboti, ara Jesreeli, ni ọgba-ajara ti o wà ni Jesreeli, ti o sunmọ ãfin Ahabu, ọba Samaria girigiri. 2 Ahabu si ba Naboti sọ wipe, Fun mi ni ọgba-ajara rẹ, ki emi ki o fi ṣe ọgba-ewebẹ̀, nitori ti o sunmọ ile mi: emi o si fun ọ li ọgba-ajara ti o san jù u lọ dipò rẹ̀; bi o ba si dara li oju rẹ, emi o fi iye-owo rẹ̀ fun ọ. 3 Naboti si wi fun Ahabu pe, Oluwa má jẹ ki emi fi ogún awọn baba mi fun ọ. 4 Ahabu si wá si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ nitori ọ̀rọ ti Naboti, ara Jesreeli, sọ fun u: nitoriti on ti wipe, emi kì o fun ọ ni ogún awọn baba mi. On si dubulẹ lori akete rẹ̀, o si yi oju rẹ̀ padà, kò si fẹ ijẹun. 5 Jesebeli, aya rẹ̀ si tọ̀ ọ wá o si wi fun u pe, Ẽṣe ti inu rẹ fi bajẹ́ ti iwọ kò fi jẹun? 6 O si wi fun u pe, Nitoriti mo ba Naboti, ara Jesreeli sọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni ọgba-àjara rẹ fun owo; tabi bi o ba wù ọ, emi o fun ọ ni ọgba-àjara miran ni ipò rẹ̀: o si dahùn wipe, Emi kì o fun ọ ni ọgba-àjara mi. 7 Jesebeli, aya rẹ̀ si wi fun u pe, iwọ kò ha jọba lori Israeli nisisiyi? Dide, jẹun, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn! emi o fun ọ ni ọgba-àjara Nãboti ara Jesreeli. 8 Bẹ̃ni o kọwe li orukọ Ahabu, o si fi èdidi rẹ̀ di i, o si fi iwe na ṣọwọ sọdọ awọn àgbagba ati awọn ọlọla ti mbẹ ni ilu rẹ̀, ti o si mba Naboti gbe. 9 O si kọ sinu iwe na pe, Ẹ kede àwẹ, ki ẹ si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia. 10 Ki ẹ fi enia meji, ẹni buburu, siwaju rẹ̀ lati jẹri pa a, wipe, Iwọ bu Ọlọrun ati ọba. Ẹ mu u jade, ki ẹ si sọ ọ li okuta ki o le kú. 11 Awọn ọkunrin ilu rẹ̀, ati awọn àgbagba, ati awọn ọlọla ti nwọn iṣe ara-ilu rẹ̀, ṣe bi Jesebeli ti ranṣẹ si wọn, gẹgẹ bi a ti kọ ọ sinu iwe ti o ti fi ranṣẹ si wọn. 12 Nwọn si kede àwẹ, nwọn si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia. 13 Ọkunrin meji si de, awọn ẹni buburu, nwọn si joko niwaju rẹ̀: awọn ọkunrin buburu si jẹri pa a, ani si Naboti, niwaju awọn enia wipe: Naboti bu Ọlọrun ati ọba. Nigbana ni nwọn mu u jade kuro ni ilu, nwọn si sọ ọ li okuta, o si kú. 14 Nigbana ni nwọn ranṣẹ si Jesebeli wipe, A sọ Naboti li okuta, o si kú. 15 O si ṣe, nigbati Jesebeli gbọ́ pe, a sọ Naboti li okuta, o si kú, Jesebeli sọ fun Ahabu pe, Dide! ki o si jogun ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli, ti o kọ̀ lati fi fun ọ fun owo; nitori Naboti kò si lãye ṣugbọn o kú. 16 O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ pe, Naboti kú, ni Ahabu dide lati sọkalẹ lọ si ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli lati jogun rẹ̀. 17 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe, 18 Dide, sọkalẹ, lọ ipade Ahabu, ọba Israeli, ti o wà ni Samaria: wò o, o wà ni ọgba-ajara Naboti, nibiti o sọkalẹ lọ lati jogun rẹ̀. 19 Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ. 20 Ahabu si wi fun Elijah pe, Iwọ ri mi, Iwọ ọta mi? O si dahùn wipe, Emi ri ọ; nitoriti iwọ ti tà ara rẹ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa. 21 Kiyesi i, Emi o mu ibi wá si ori rẹ, emi o si mu iran rẹ kuro, emi o si ke kuro lọdọ Ahabu, gbogbo ọmọde ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ, ati omnira ni Israeli. 22 Emi o si ṣe ile rẹ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa, ọmọ Ahijah, nitori imunibinu ti iwọ ti mu mi binu, ti iwọ si mu ki Israeli ki o dẹ̀ṣẹ. 23 Ati niti Jesebeli pẹlu Oluwa sọ wipe, Awọn ajá yio jẹ Jesebeli ninu yàra Jesreeli. 24 Ẹni Ahabu ti o kú ni ilu, ni awọn ajá o jẹ; ati ẹniti o kú ni igbẹ ni awọn ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ. 25 Ṣugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rẹ̀ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rẹ̀ ntì. 26 O si ṣe ohun irira gidigidi ni titọ̀ oriṣa lẹhin, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awọn ara Amori ti ṣe, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli. 27 O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si gbàwẹ, o si dubulẹ ninu aṣọ ọ̀fọ, o si nlọ jẹ́. 28 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe, 29 Iwọ ri bi Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi? Nitori ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi, emi kì yio mu ibi na wá li ọjọ rẹ̀: li ọjọ ọmọ rẹ̀ li emi o mu ibi na wá sori ile rẹ̀.

1 Ọba 22

Wolii Mikaaya Kìlọ̀ fún Ahabu

1 ỌDUN mẹta si rekọja laisi ogun lãrin Siria ati lãrin Israeli. 2 O si ṣe li ọdun kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda sọkalẹ tọ ọba Israeli wá. 3 Ọba Israeli si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin ha mọ̀ pe, tiwa ni Ramoti-Gileadi, awa si dakẹ, a kò si gbà a kuro lọwọ ọba Siria? 4 O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ. 5 Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Mo bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa li oni yi. 6 Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ. 7 Jehoṣafati si wipe, Kò si woli Oluwa kan nihin pẹlu, ti awa iba bère lọwọ rẹ̀? 8 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃. 9 Ọba Israeli si pè iwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah, ọmọ Imla, ki o yara wá. 10 Ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda joko olukulùku lori itẹ́ rẹ̀, nwọn wọ̀ aṣọ igunwa wọn ni ita ẹnu-bode Samaria, gbogbo awọn woli na si nsọtẹlẹ niwaju wọn. 11 Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn. 12 Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe: Goke lọ si Ramoti-Gileadi, ki o si ṣe rere: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ. 13 Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnu kanna ni ọ̀rọ awọn woli fi jẹ rere fun ọba: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọ̀rọ ọkan ninu wọn, ki o si sọ rere. 14 Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti wà, ohun ti Oluwa ba sọ fun mi li emi o sọ. 15 Bẹ̃ni o de ọdọ ọba. Ọba si wi fun u pe, Mikaiah, ki awa o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki a jọwọ rẹ̀? O si da a lohùn pe, Lọ, ki o si ṣe rere: nitori Oluwa yio fi i le ọba lọwọ. 16 Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bu pe, ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikoṣe otitọ li orukọ Oluwa? 17 On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia. 18 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò sọ fun ọ, pe on kì o fọ̀ ire si mi, bikoṣe ibi? 19 On si wipe, Nitorina, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun-ọrun duro li apa ọtun ati li apa òsi rẹ̀. 20 Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ki o le goke lọ, ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ẹnikan si wi bayi, ẹlomiran si sọ miran. 21 Ẹmi kan si jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a. 22 Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃. 23 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi-eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ. 24 Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana sunmọ ọ, o si lu Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ? 25 Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o lọ lati inu iyẹwu de iyẹwu lati fi ara rẹ pamọ. 26 Ọba Israeli si wipe, Mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba: 27 Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi: Ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi onjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia. 28 Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ipa mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!

Ikú Ahabu

29 Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, goke lọ si Ramoti-Gileadi. 30 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà. 31 Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan. 32 O si ṣe, bi awọn olori-kẹkẹ́ ti ri Jehoṣafati, nwọn si wipe, ọba Israeli li eyi. Nwọn si yà sapakan lati ba a jà: Jehoṣafati si kigbe. 33 O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ woye pe, kì iṣe ọba Israeli li eyi, nwọn si pada kuro lẹhin rẹ̀. 34 Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ. 35 Ogun na si le li ọjọ na: a si dá ọba duro ninu kẹkẹ́ kọju si awọn ara Siria, o si kú li aṣalẹ, ẹ̀jẹ si ṣàn jade lati inu ọgbẹ na si ãrin kẹkẹ́ na. 36 A si kede la ibudo já li akokò iwọ̀ õrun wipe, Olukuluku si ilu rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀. 37 Bẹ̃ni ọba kú, a si gbe e wá si Samaria; nwọn si sin ọba ni Samaria. 38 Ẹnikan si wẹ kẹkẹ́ na ni adagun Samaria, awọn ajá si la ẹ̀jẹ rẹ̀; awọn àgbere si wẹ ara wọn ninu rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ, 39 Ati iyokù iṣe Ahabu, ati gbogbo eyi ti o ṣe, ati ile ehin-erin ti o kọ́, ati gbogbo ilu ti o tẹ̀do, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 40 Ahabu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Ahasiah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Jehoṣafati, Ọba Juda

41 Jehoṣafati, ọmọ Asa, si bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda li ọdun kẹrin Ahabu, ọba Israeli. 42 Jehoṣafati si to ẹni ọdun marundilogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mẹ̃dọgbọn ni Jerusalẹmu. Orukọ iya rẹ̀ ni Asuba ọmọbinrin Ṣilhi. 43 O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni. 44 Jehoṣafati si wà li alafia pẹlu ọba Israeli. 45 Ati iyokù iṣe Jehoṣafati ati iṣe agbara rẹ̀ ti o ṣe, ati bi o ti jagun si, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 46 Iyokù awọn ti nhuwà panṣaga ti o kù li ọjọ Asa baba rẹ̀, li o parun kuro ni ilẹ na. 47 Nigbana kò si ọba ni Edomu: adelé kan li ọba. 48 Jehoṣafati kàn ọkọ̀ Tarṣiṣi lati lọ si Ofiri fun wura; ṣugbọn nwọn kò lọ: nitori awọn ọkọ̀ na fọ́ ni Esion-Geberi. 49 Nigbana ni Ahasiah, ọmọ Ahabu, wi fun Jehoṣafati pe, Jẹ ki awọn iranṣẹ mi ba awọn iranṣẹ rẹ lọ ninu ọkọ̀. Ṣugbọn Jehoṣafati kọ̀. 50 Jehoṣafati si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi, baba rẹ̀: Jehoramu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Ahasaya, Ọba Israẹli

51 Ahasiah, ọmọ Ahabu, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kẹtadilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun meji lori Israeli. 52 O si ṣe ibi niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati li ọ̀na iya rẹ̀, ati li ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ: 53 Nitoriti o sin Baali, o si mbọ ọ, o si mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.

2 Ọba 1

Elija ati Ọba Ahasaya

1 NIGBANA ni Moabu ṣọ̀tẹ si Israeli lẹhin ikú Ahabu. 2 Ahasiah si ṣubu lãrin fèrese ọlọnà kan ni iyara òke rẹ̀ ti o wà ni Samaria, o si ṣàisan: o si rán awọn onṣẹ o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, bi emi o là ninu aisan yi. 3 Ṣugbọn angeli Oluwa wi fun Elijah, ara Tiṣbi pe, Dide, gòke lọ ipade awọn onṣẹ ọba Samaria, ki o si wi fun wọn pe, Kò ṣe pe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni ẹnyin fi nlọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? 4 Njẹ nitorina bayi li Oluwa wi, Iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì lori eyiti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú. Elijah si lọ kuro. 5 Nigbati awọn onṣẹ si pada si ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi pada sẹhin? 6 Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan li o gòke lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ pada tọ̀ ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? nitorina, iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú. 7 On si wi fun wọn pe, Iru ọkunrin wo li ẹniti o gòke lati pade nyin, ti o si sọ̀rọ wọnyi fun nyin? 8 Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni. 9 Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ. 10 Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀. 11 On si tun rán olori-ogun ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, Bayi li ọba wi, yara sọ̀kalẹ. 12 Elijah si dahùn, o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o si run ọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọrun si sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀. 13 O si tun rán olori-ogun ãdọta ekẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori-ogun ãdọta kẹta si gòke, o si wá, o si wolẹ lori ẽkún rẹ̀ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Iwọ, enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ́, jẹ ki ẹmi mi ati ẹmi awọn ãdọta ọmọ-ọdọ rẹ wọnyi, ki o ṣọwọn li oju rẹ. 14 Kiyesi i, iná sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run olori-ogun meji arãdọta iṣãju pẹlu arãdọta wọn: njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹmi mi ki o ṣọwọn li oju rẹ. 15 Angeli Oluwa si wi fun Elijah pe, Ba a sọ̀kalẹ lọ: máṣe bẹ̀ru rẹ̀. On si dide, o si ba a sọ̀kalẹ lọ sọdọ ọba. 16 On si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ ran onṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli lati bère ọ̀rọ rẹ̀? nitorina iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú; 17 Bẹ̃ni o kú gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti Elijah ti sọ. Jehoramu si jọba ni ipò rẹ̀, li ọdun keji Jehoramu ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda, nitoriti kò ni ọmọkunrin. 18 Ati iyokù iṣe Ahasiah ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

2 Ọba 2

A gbé Elija lọ sọ́run

1 O si ṣe, nigbati Oluwa nfẹ lati fi ãjà gbé Elijah lọ si òke ọrun, ni Elijah ati Eliṣa lọ kuro ni Gilgali. 2 Elijah si wi fun Eliṣa pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Beteli. Eliṣa si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn sọ̀kalẹ lọ si Beteli. 3 Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Beteli jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́. 4 Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitori ti Oluwa rán mi si Jeriko. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn de Jeriko. 5 Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Jeriko tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́. 6 Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ. 7 Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani. 8 Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ. 9 O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi. 10 On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃. 11 O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, ti nwọn nsọ̀rọ, si kiyesi i, kẹkẹ́ iná ati ẹṣin iná si là ãrin awọn mejeji; Elijah si ba ãjà gòke re ọrun. 12 Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On kò si ri i mọ: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji. 13 On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si pada sẹhin, o si duro ni bèbe Jordani. 14 On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun Elijah wà? Nigbati on pẹlu si lù omi na, nwọn si pinyà sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja. 15 Awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Jeriko nihà keji si ri i, nwọn si wipe, Ẹmi Elijah bà le Eliṣa. Nwọn si wá ipade rẹ̀; nwọn si tẹ̀ ara wọn ba silẹ niwaju rẹ̀. 16 Nwọn si wi fun u pe, Wò o na, ãdọta ọkunrin alagbara mbẹ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ; awa bẹ̀ ọ, jẹ ki nwọn ki o lọ, ki nwọn ki o si wá oluwa rẹ lọ: bọya Ẹmi Oluwa ti gbé e sokè, o si ti sọ ọ sori ọkan ninu òke nla wọnni, tabi sinu afonifojì kan. On si wipe, Ẹ máṣe ranṣẹ. 17 Nigbati nwọn si rọ̀ ọ titi oju fi tì i, o wi fun wọn pe, Ranṣẹ. Nitorina nwọn rán ãdọta ọkunrin, nwọn si wá a ni ijọ mẹta, ṣugbọn nwọn kò ri i. 18 Nwọn si tun pada tọ̀ ọ wá, (nitori ni Jeriko li o joko,) o wi fun wọn pe, Emi kò ti wi fun nyin pe, Ẹ máṣe lọ?

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Eliṣa

19 Awọn ọkunrin ilu na si wi fun Eliṣa pe, Kiyesi i, itẹ̀do ilu yi dara, bi oluwa mi ti ri i: ṣugbọn omi buru, ilẹ si ṣá. 20 On si wipe, Mu àwokóto titun kan fun mi wá, si fi iyọ̀ sinu rẹ̀; nwọn si mu u tọ̀ ọ wá. 21 On si jade lọ si ibi orisun omi na, o si dà iyọ na sibẹ, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ṣe àwotan omi wọnyi; lati ihin lọ, kì yio si ikú mọ, tabi aṣálẹ. 22 Bẹ̃ni a ṣe àwotan omi na titi di oni oloni, gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa ti o sọ. 23 O si gòke lati ibẹ lọ si Beteli: bi o si ti ngòke lọ li ọ̀na, awọn ọmọ kekeke jade lati ilu wá, nwọn si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si wi fun u pe, Gòke lọ, apari! gòke lọ, apari! 24 O si yipada, o si wò wọn, o si fi wọn bú li orukọ Oluwa. Abo-beari meji si jade lati inu igbó wá, nwọn si fà mejilelogoji ya ninu wọn. 25 O si ti ibẹ lọ si òke Karmeli; ati lati ibẹ o pada si Samaria.

2 Ọba 3

Ogun láàrin Israẹli ati Moabu

1 JEHORAMU, ọmọ Ahabu si bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kejidilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun mejila. 2 O si ṣe buburu li oju Oluwa; ṣugbọn kì iṣe bi baba rẹ̀, ati bi iya rẹ̀: nitoriti o mu ere Baali ti baba rẹ̀ ti ṣe kuro. 3 Ṣugbọn o fi ara mọ ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ; kò si lọ kuro ninu rẹ̀. 4 Meṣa, ọba Moabu si nsìn agutan, o si nsan ọkẹ marun ọdọ-agutan, ati ọkẹ marun àgbo irun fun ọba Israeli. 5 O si ṣe, nigbati Ahabu kú, ọba Moabu si ṣọ̀tẹ si ọba Israeli. 6 Jehoramu ọba si jade lọ kuro ni Samaria li akoko na, o si ka iye gbogbo Israeli. 7 O si lọ, o ranṣẹ si Jehoṣafati ọba Juda, wipe, Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ si mi: iwọ o ha bá mi lọ si Moabu lati jagun? On si wipe, Emi o gòke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ. 8 On si wipe, Ọ̀na wo li awa o gbà gòke lọ? On si dahùn wipe, Ọ̀na aginju Edomu. 9 Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin. 10 Ọba Israeli si wipe, O ṣe! ti Oluwa fi pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ! 11 Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi. 12 Jehoṣafati si wipe, Ọ̀rọ Oluwa mbẹ pẹlu rẹ̀. Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati ati ọba Edomu sọ̀kalẹ tọ̀ ọ lọ. 13 Eliṣa si wi fun ọba Israeli pe, Kini o ṣe mi ṣe ọ? Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃kọ: nitori ti Oluwa ti pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ. 14 Eliṣa si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, iba má ṣepe mo bu ọwọ Jehoṣafati ọba Juda, nitõtọ emi kì ba ti bẹ̀ ọ wò, bẹ̃ni emi kì ba ti ri ọ. 15 Ṣugbọn ẹ mu akọrin kan fun mi wá nisisiyi. O si ṣe, nigbati akọrin na nkọrin, ọwọ Oluwa si bà le e. 16 On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wà iho pupọ li afonifojì yi. 17 Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin. 18 Ohun kikini si li eyi loju Oluwa: on o fi awọn ara Moabu le nyin lọwọ pẹlu. 19 Ẹnyin o si kọlù gbogbo ilu olodi, ati gbogbo ãyò ilu, ẹnyin o si ké gbogbo igi rere lulẹ, ẹnyin o si dí gbogbo kanga omi, ẹnyin o si fi okuta bà gbogbo oko rere jẹ. 20 O si ṣe li owurọ, bi a ti nta ọrẹ-ẹbọ onjẹ, si kiyesi i, omi ti ọ̀na Edomu wá, ilẹ na si kún fun omi. 21 Nigbati gbogbo ara Moabu gbọ́ pe, awọn ọba gòke wá lati ba wọn jà, nwọn kó gbogbo awọn ti o le hamọra ogun jọ, ati awọn ti o dagba jù wọn lọ, nwọn si duro li eti ilẹ wọn. 22 Nwọn si dide li owurọ̀, õrùn si ràn si oju omi na, awọn ara Moabu si ri omi na li apakeji, o pọn bi ẹ̀jẹ: 23 Nwọn si wipe, Ẹ̀jẹ li eyi: awọn ọba na run: nwọn si ti pa ara wọn; njẹ nisisiyi, Moabu, dide si ikogun. 24 Nigbati nwọn si de ibùdo Israeli, awọn ọmọ Israeli dide, nwọn si kọlù awọn ara Moabu, nwọn si sa kuro niwaju wọn: nwọn si wọ inu rẹ̀, nwọn si pa Moabu run. 25 Nwọn si wó gbogbo ilu, olukulùku si jù okuta tirẹ̀ si gbogbo oko rere, nwọn si kún wọn; nwọn si dí gbogbo kanga omi, nwọn si bẹ́ gbogbo igi rere: ni Kirharaseti ni nwọn fi kiki awọn okuta rẹ̀ silẹ ṣugbọn awọn oni-kànakana yi i ka, nwọn si kọlù u. 26 Nigbati ọba Moabu ri i pe ogun na le jù fun on, o mu ẹ̃dẹgbẹrin ọkunrin ti o fà idà yọ pẹlu rẹ̀, lati là ogun ja si ọdọ ọba Edomu: ṣugbọn nwọn kò le ṣe e. 27 Nigbana li o mu akọbi ọmọ rẹ̀ ti iba jọba ni ipò rẹ̀, o si fi i rubọ sisun li ori odi. Ibinu nla si wà si Israeli: nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, nwọn si pada si ilẹ wọn.

2 Ọba 4

Eliṣa Ran Opó Aláìní Kan Lọ́wọ́

1 OBIRIN kan ninu awọn obinrin ọmọ awọn woli ke ba Eliṣa wipe, Iranṣẹ rẹ, ọkọ mi kú; iwọ si mọ̀ pe iranṣẹ rẹ bẹ̀ru Oluwa: awọn onigbèse si wá lati mu awọn ọmọ mi mejeji li ẹrú. 2 Eliṣa si wi fun u pe, Kini emi o ṣe fun ọ? Wi fun mi, kini iwọ ni ninu ile? On si wipe, Iranṣẹbinrin rẹ kò ni nkankan ni ile, bikòṣe ikòko ororo kan. 3 On si wipe, Lọ, ki iwọ ki o yá ikòko lọwọ awọn aladugbò rẹ kakiri, ani ikòko ofo; yá wọn, kì iṣe diẹ. 4 Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹ̀kun mọ ara rẹ, ati mọ awọn ọmọ rẹ, ki o si dà a sinu gbogbo ikòko wọnni, ki iwọ ki o si fi eyiti o kún si apakan. 5 O si lọ kuro lọdọ rẹ̀, o si se ilẹ̀kun mọ ara rẹ̀ ati mọ awọn ọmọ rẹ̀, ti ngbe ikòko fun u wá; on si dà a. 6 O si ṣe, nigbati awọn ikòko kún, o wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Tun mu ikòko kan fun mi wá. On si wi fun u pe, Kò si ikòko kan mọ. Ororo na si da. 7 Nigbana li o wá, o si sọ fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Lọ, tà ororo na, ki o si san gbèse rẹ, ki iwọ ati awọn ọmọ rẹ ki o si jẹ eyi ti o kù.

Eliṣa ati Obinrin Ọlọ́rọ̀ Ará Ṣunemu

8 O si di ọjọ kan, Eliṣa si kọja si Ṣunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wà; on si rọ̀ ọ lati jẹ onjẹ. O si ṣe, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a yà si ibẹ lati jẹ onjẹ. 9 On si wi fun ọkọ rẹ̀ pe, Sa wò o na, emi woye pe, enia mimọ́ Ọlọrun li eyi ti ngbà ọdọ wa kọja nigbakugba. 10 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a ṣe yàrá kekere kan lara ogiri; si jẹ ki a gbe ibùsùn kan sibẹ fun u, ati tabili kan, ati ohun-ijoko kan, ati ọpá-fitila kan: yio si ṣe, nigbati o ba tọ̀ wa wá, ki on ma wọ̀ sibẹ. 11 O si di ọjọ kan, ti o wá ibẹ̀, o si yà sinu yàrá na, o si dubulẹ nibẹ. 12 On si wi fun Gehasi iranṣẹ rẹ̀ pe, Pè ara Ṣunemu yi. Nigbati o si pè e, o duro niwaju rẹ̀. 13 On si wi fun u pe, nisisiyi, sọ fun u pe, Kiyesi i, iwọ ti fi gbogbo itọju yi ṣe aniyàn wa; kini a ba ṣe fun ọ? Iwọ nfẹ́ ki a sọ̀rọ rẹ fun ọba bi? tabi fun olori-ogun? On si dahùn wipe, Emi ngbe lãrin awọn enia mi. 14 On si wipe, Njẹ kini a ba ṣe fun u? Gehasi si dahùn pe, Nitõtọ, on kò li ọmọ, ọkọ rẹ̀ si di arugbo. 15 On si wipe, Pè e wá, nigbati o si ti pè e de, o duro li ẹnu-ọ̀na. 16 On si wipe, Li akokò yi gẹgẹ bi igba aiye, iwọ gbé ọmọkunrin kan mọra. On si wipe, Bẹ̃kọ̀, oluwa mi, iwọ enia Ọlọrun, má ṣe purọ fun iranṣẹbinrin rẹ. 17 Obinrin na si loyun, o si bi ọmọkunrin kan li akokò na ti Eliṣa ti sọ fun u, gẹgẹ bi igba aiye. 18 Nigbati ọmọ na si dagba, o di ọjọ kan, ti o jade tọ̀ baba rẹ̀ lọ si ọdọ awọn olukore. 19 O si wi fun baba rẹ̀ pe, Ori mi, ori mi! On si sọ fun ọmọ-ọdọ̀ kan pe, Gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ. 20 Nigbati o si gbé e, ti o mu u tọ̀ iya rẹ̀ wá, o joko li ẽkun rẹ̀ titi di ọjọ kanri, o si kú. 21 On si gòke, o si tẹ́ ẹ sori ibùsun enia Ọlọrun na, o si sé ilẹ̀kun mọ ọ, o si jade lọ. 22 On si ke si ọkọ rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, rán ọkan ninu awọn ọdọmọkunrin si mi, ati ọkan ninu awọn kẹtẹkẹtẹ, emi o si sare tọ̀ enia Ọlọrun lọ, emi o si tun pada. 23 On si wipe, Ẽṣe ti iwọ o fi tọ̀ ọ lọ loni? kì isa ṣe oṣù titun, bẹ̃ni kì iṣe ọjọ isimi. On sì wipe, Alafia ni. 24 Nigbana li o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, o si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Mã le e, ki o si ma nṣo; máṣe dẹ̀ ire fun mi, bikòṣepe mo sọ fun ọ. 25 Bẹ̃li o lọ, o si de ọdọ enia Ọlọrun na li òke Karmeli. O si ṣe, nigbati enia Ọlọrun na ri i li okère, o si sọ fun Gehasi ọmọ ọdọ rẹ̀ pe, Wò ara Ṣunemu nì: 26 Emi bẹ̀ ọ, sure nisisiyi ki o pade rẹ̀, ki o si wi fun u pe, Alafia ki o wà bi? alafia ki ọkọ rẹ̀ wà bi? alafia ki ọmọde wà bi? On si dahùn wipe, Alafia ni. 27 Nigbati o si de ọdọ enia Ọlọrun li ori òke, o gbá a li ẹsẹ̀ mu: ṣugbọn Gehasi sunmọ ọ lati tì i kurò. Enia Ọlọrun na si wipe, Jọwọ rẹ̀ nitori ọkàn rẹ̀ bajẹ ninu rẹ̀, Oluwa si pa a mọ́ fun mi, kò si sọ fun mi. 28 Nigbana li o wipe, Mo ha tọrọ ọmọ li ọwọ oluwa mi bi? Emi kò ha wipe, Máṣe tàn mi jẹ? 29 O si wi fun Gehasi pe, Di àmure rẹ, ki o si mu ọpa mi li ọwọ rẹ, ki o si lọ, bi iwọ ba ri ẹnikẹni li ọ̀na, máṣe ki i; bi ẹnikeni ba si kí ọ, máṣe da a li ohùn: ki o si fi ọpá mi le iwaju ọmọ na. 30 Iya ọmọ na si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. On si dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin. 31 Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji. 32 Nigbati Eliṣa si wọ̀ inu ile, kiyesi i, ọmọ na ti kú, a si tẹ́ ẹ sori ibùsun rẹ̀. 33 O si wọ̀ inu ile lọ, o si se ilẹ̀kun mọ awọn mejeji, o si gbadura si Oluwa. 34 On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná. 35 O si pada, o si rìn lọ, rìn bọ̀ ninu ile lẹ̃kan; o si gòke, o si nà ara rẹ̀ le e; ọmọ na si sín nigba meje; ọmọ na si là oju rẹ̀. 36 O si pè Gehasi, o si wipe, Pè ara Ṣunemu yi wá. O si pè e. Nigbati o si wọle tọ̀ ọ wá, o ni, Gbé ọmọ rẹ. 37 Nigbana li o wọ̀ inu ile, o si wolẹ li ẹba ẹṣẹ̀ rẹ̀, o si dojubolẹ, o si gbé ọmọ rẹ̀, o si jade lọ.

Iṣẹ́ Ìyanu Meji Mìíràn

38 Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli. 39 Ẹnikan si jade lọ si igbẹ lati fẹ́ ewebẹ̀, o si ri ajara-igbẹ kan, o si ka eso rẹ̀ kún aṣọ rẹ̀, o si rẹ́ ẹ wẹwẹ, o dà wọn sinu ikoko ipẹ̀tẹ na: nitoripe nwọn kò mọ̀ wọn. 40 Bẹ̃ni nwọn si dà a fun awọn ọkunrin na lati jẹ. O si ṣe bi nwọn ti njẹ ipẹ̀tẹ na, nwọn si kigbe, nwọn si wipe, Iwọ enia Ọlọrun, ikú mbẹ ninu ikoko na! Nwọn kò si le jẹ ẹ. 41 Ṣugbọn on wipe, Njẹ, ẹ mu iyẹ̀fun wá. O si dà a sinu ikoko na, o si wipe, Dà a fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. Kò si si jamba ninu ikoko mọ. 42 Ọkunrin kan si ti Baali-Ṣaliṣa wá, o si mu àkara akọso-eso, ogun iṣu àkara barle, ati ṣiri ọkà titun ninu àpo rẹ̀ wá fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. 43 Iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kinla, ki emi ki o gbé eyi kà iwaju ọgọrun enia? On si tun wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ: nitori bayi li Oluwa wi pe, Nwọn o jẹ, nwọn o si kù silẹ. 44 Bẹ̃li o gbe e kà iwaju wọn, nwọn si jẹ, nwọn si kù silẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

2 Ọba 5

Naamani Gba Ìwòsàn

1 NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni. 2 Awọn ara Siria si ti jade lọ ni ẹgbẹ́-ẹgbẹ́, nwọn si ti mu ọmọbinrin kekere kan ni igbèkun lati ilẹ Israeli wá; on si duro niwaju obinrin Naamani. 3 On si wi fun iya rẹ̀ pe, oluwa mi iba wà niwaju woli ti mbẹ ni Samaria! nitõtọ on iba wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀. 4 On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi. 5 Ọba Siria si wipe, Wá na, lọ, emi o si fi iwe ranṣẹ si ọba Israeli. On si jade lọ, o si mu talenti fàdakà mẹwa lọwọ, ati ẹgbãta iwọ̀n wurà, ati ipãrọ aṣọ mẹwa. 6 On si mu iwe na tọ̀ ọba Israeli wá, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba de ọdọ rẹ, kiyesi i, emi rán Naamani iranṣẹ mi si ọ, ki iwọ ki o le wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀. 7 O si ṣe, nigbati ọba Israeli kà iwe na tan, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Emi ha iṣe Ọlọrun, lati pa ati lati sọ di ãyè, ti eleyi fi ranṣẹ si mi lati ṣe awòtan enia kan kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀? nitorina, ẹ rò o wò, mo bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò o bi on ti nwá mi ni ijà. 8 O si ṣe, nigbati Eliṣa enia Ọlọrun gbọ́ pe, ọba Israeli fà aṣọ rẹ̀ ya, o si ranṣẹ si ọba wipe, Ẽṣe ti iwọ fi fà aṣọ rẹ ya? jẹ ki o tọ̀ mi wá nisisiyi, on o si mọ̀ pe, woli kan mbẹ ni Israeli. 9 Bẹ̃ni Naamani de pẹlu awọn ẹṣin rẹ̀ ati pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀, o si duro li ẹnu-ọ̀na ile Eliṣa. 10 Eliṣa si ràn iranṣẹ kan si i wipe, Lọ, ki o si wẹ̀ ni Jordani nigba meje, ẹran-ara rẹ yio si tun bọ̀ sipò fun ọ, iwọ o si mọ́. 11 Ṣugbọn Naamani binu, o si pada lọ, o si wipe, Kiyesi, i, mo rò ninu mi pe, dajudaju on o jade tọ̀ mi wá, yio si duro, yio si kepè orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, yio si fi ọwọ rẹ̀ pa ibẹ̀ na, yio si ṣe awòtan ẹ̀tẹ na. 12 Abana ati Farpari, awọn odò Damasku kò ha dara jù gbogbo awọn omi Israeli lọ? emi kì iwẹ̀ ninu wọn ki emi si mọ́? Bẹ̃li o yipada, o si jade lọ ni irúnu. 13 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sunmọ ọ, nwọn si ba a sọ̀rọ, nwọn si wipe, Baba mi, woli iba wi fun ọ pe, ki o ṣe ohun nla kan, iwọ kì ba ti ṣe e bi? melomelo, nigbati o wi fun ọ pe, Wẹ̀, ki o si mọ́? 14 Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́. 15 O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ. 16 Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀. 17 Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa. 18 Ninu nkan yi ni ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ, nigbati oluwa mi ba lọ si ile Rimmoni lati foribalẹ nibẹ, ti on ba si fi ara tì ọwọ mi, ti emi tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni: nigbati mo ba tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni, ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ ninu nkan yi. 19 On si wi fun u pe, Mã lọ ni alãfia. Bẹ̃ni o si jade lọ jinà diẹ kuro lọdọ rẹ̀. 20 Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀. 21 Bẹ̃ni Gehasi lepa Naamani. Nigbati Naamani ri ti nsare bọ̀ lẹhin on, o sọ̀kalẹ kuro ninu kẹkẹ́ lati pade rẹ̀, o si wipe, Alafia kọ? 22 On si wipe, Alafia ni. Oluwa mi rán mi, wipe, Kiyesi i, nisisiyi ni ọdọmọkunrin meji ninu awọn ọmọ woli ti òke Efraimu wá ọdọ mi; emi bẹ̀ o, fun wọn ni talenti fadakà kan, ati ipàrọ aṣọ meji. 23 Naamani si wipe, Fi ara balẹ, gbà talenti meji. O si rọ̀ ọ, o si dì talenti fadakà meji sinu apò meji, pẹlu ipàrọ aṣọ meji, o si gbé wọn rù ọmọ-ọdọ rẹ̀ meji; nwọn si rù wọn niwaju rẹ̀. 24 Nigbati o si de ibi ile ìṣọ, o gbà wọn lọwọ wọn, o si tò wọn sinu ile: o si jọ̀wọ awọn ọkunrin na lọwọ lọ, nwọn si jade lọ. 25 Ṣugbọn on wọ̀ inu ile lọ, o si duro niwaju oluwa rẹ̀. Eliṣa si wi fun u pe, Gehasi, nibo ni iwọ ti mbọ̀? On si wipe, Iranṣẹ rẹ kò lọ ibikibi. 26 On si wi fun u pe, Ọkàn mi kò ha ba ọ lọ, nigbati ọkunrin na fi yipada kuro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ lati pade rẹ? Eyi ha iṣe akokò ati gbà fadakà, ati lati gbà aṣọ, ati ọgbà-olifi ati ọgbà-ajara, ati àgutan, ati malu, ati iranṣékunrin ati iranṣẹbinrin? 27 Nitorina ẹ̀tẹ Naamani yio lẹ mọ ọ, ati iru-ọmọ rẹ titi lai. On si jade kuro niwaju rẹ̀, li adẹtẹ̀ ti o funfun bi ojodidì.

2 Ọba 6

Irin Àáké Léfòó

1 AWỌN ọmọ awọn woli wi fun Eliṣa pe, Sa wò o na, ibiti awa gbe njoko niwaju rẹ, o há jù fun wa. 2 Jẹ ki awa ki o lọ, awa bẹ̀ ọ, si Jordani, ki olukulùku wa ki o mu iti igi kọ̃kan wá, si jẹ ki awa ki o ṣe ibikan, ti awa o ma gbe. On si dahùn wipe, Ẹ mã lọ. 3 Ẹnikan si wipe, Ki o wu ọ, emi bẹ̀ ọ, lati ba awọn iranṣẹ rẹ lọ. On si dahùn pe, Emi o lọ. 4 Bẹ̃li o ba wọn lọ. Nigbati nwọn si de Jordani, nwọn ké igi. 5 O si ṣe, bi ẹnikan ti nké iti-igi, ãke yọ sinu omi: o si kigbe, o si wipe, Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rẹ̀ ni. 6 Enia Ọlọrun si wipe, Nibo li o bọ́ si? O si fi ibẹ hàn a. On si ké igi kan, o si sọ́ ọ sinu rẹ̀; irin na si fó soke. 7 Nitorina o wipe, Mu u. On si nà ọwọ rẹ̀, o si mu u.

Israẹli Ṣẹgun Siria

8 Nigbana ni ọba Siria mba Israeli jagun, o si ba awọn iranṣẹ rẹ̀ gbèro wipe, Ni ibi bayibayi ni ibùba mi yio gbe wà. 9 Enia Ọlọrun si ranṣẹ si ọba Israeli wipe Kiye sara, ki iwọ ki o máṣe kọja si ibi bayi; nitori nibẹ ni awọn ara Siria ba si. 10 Ọba Israeli si ranṣẹ si ibẹ na ti enia Ọlọrun ti sọ fun u, ti o si ti kilọ fun u, o si gbà ara rẹ̀ nibẹ, kì iṣe nigbà kan tabi nigba meji. 11 Nitorina li ọkàn ọba Siria bajẹ gidigidi nitori nkan yi: o si pè awọn iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin kì yio ha fihan mi, tani ninu wa ti o nṣe ti ọba Israeli? 12 Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kò si ẹnikan, oluwa mi, ọba; bikoṣe Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israeli, ni nsọ fun ọba Israeli gbogbo ọ̀rọ ti iwọ nsọ ninu iyẹ̀wu rẹ. 13 On si wipe, Ẹ lọ iwò ibi ti on gbe wà, ki emi o le ranṣẹ lọ mu u wá. A si sọ fun u, wipe, Wò o, o wà ni Dotani. 14 Nitorina li o ṣe rán awọn ẹṣin ati kẹkẹ́ ati ogun nla sibẹ: nwọn si de li oru, nwọn si yi ilu na ka. 15 Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe? 16 On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ. 17 Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka. 18 Nigbati nwọn si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, Eliṣa gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, bù ifọju lù awọn enia yi. On si bù ifọju lù wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa. 19 Eliṣa si wi fun wọn pe, Eyi kì iṣe ọ̀na, bẹ̃ni eyi kì iṣe ilu na: ẹ ma tọ̀ mi lẹhin, emi o si mu nyin wá ọdọ ọkunrin ti ẹnyin nwá. O si ṣe amọ̀na wọn lọ si Samaria. 20 O si ṣe, nigbati nwọn de Samaria ni Eliṣa wipe, Oluwa la oju awọn enia wọnyi, ki nwọn ki o lè riran. Oluwa si là oju wọn; nwọn si riran; si kiyesi i, nwọn mbẹ li ãrin Samaria. 21 Ọba Israeli si wi fun Eliṣa, nigbati o ri wọn pe, Baba mi, ki emi ki o mã pa wọn bi? ki emi ki o mã pa wọn bi? 22 On si dahùn pe, Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ, ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ̀ oluwa wọn lọ. 23 On si pèse ọ̀pọlọpọ onjẹ fun wọn; nigbati nwọn si ti jẹ, ti nwọn si ti mu tan, o rán wọn lọ, nwọn si tọ̀ oluwa wọn lọ. Bẹ̃ni ẹgbẹ́ ogun Siria kò tun wá si ilẹ Israeli mọ.

Ogun Dóti Samaria

24 O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria. 25 Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun. 26 O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba! 27 On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti? 28 Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ọ? On si dahùn wipe, Obinrin yi wi fun mi pe, Mu ọmọkunrin rẹ wá, ki awa ki o le jẹ ẹ loni, awa o si jẹ ọmọ ti emi li ọla. 29 Bẹ̃ni awa sè ọmọ mi, awa si jẹ ẹ́: emi si wi fun u ni ijọ keji pe, Mu ọmọ rẹ wá ki awa ki o jẹ́ ẹ; on si ti fi ọmọ rẹ̀ pamọ́. 30 O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ obinrin na, o fà aṣọ rẹ̀ ya; o si kọja lọ lori odi, awọn enia si wò, si kiyesi i, o ni aṣọ-ọfọ̀ labẹ aṣọ rẹ̀ li ara rẹ̀. 31 Nigbana ni o wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe bayi ati jù bẹ̃ lọ si mi, bi ori Eliṣa ọmọ Ṣafati yio duro li ọrùn rẹ̀ li oni. 32 Ṣugbọn Eliṣa joko ninu ile rẹ̀, ati awọn àgbagba joko pẹlu rẹ̀; ọba si rán ọkunrin kan ṣãju rẹ̀ lọ: ṣugbọn ki iranṣẹ na ki o to dé ọdọ rẹ̀, on wi fun awọn àgbagba pe, Ẹ wò bi ọmọ apania yi ti ranṣẹ lati mu ori mi kuro? ẹ wò, nigbati iranṣẹ na ba de, ẹ tì ilẹ̀kun, ki ẹ si dì i mu ṣinṣin li ẹnu-ọ̀na: iro-ẹsẹ̀ oluwa rẹ̀ kò ha wà lẹhin rẹ̀? 33 Bi on ti mba wọn sọ̀rọ lọwọ, kiyesi i, iranṣẹ na sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá: on si wipe, Wò o, lati ọwọ Oluwa ni ibi yi ti wá, kili emi o ha duro dè Oluwa mọ si?

2 Ọba 7

1 NIGBANA ni Eliṣa wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Bayi li Oluwa wi, Ni iwòyi ọla li a o ta oṣùwọn iyẹ̀fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria. 2 Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ sé ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.

Ogun Siria pada Sílé

3 Adẹtẹ̀ mẹrin kan si wà ni atiwọ̀ bodè; nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú? 4 Bi awa ba wipe, Awa o wọ̀ ilu lọ, iyàn si mbẹ ni ilu, awa o si kú nibẹ: bi awa ba si joko jẹ nihinyi, awa o kú pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki awa ki o ṣubu si ọwọ ogun awọn ara Siria: bi nwọn ba dá wa si, awa o yè: bi nwọn ba si pa wa, awa o kú na ni. 5 Nwọn si dide li afẹ̀mọjumọ lati lọ si ibùdo awọn ara Siria: nigbati nwọn si de apa ti o kangun ibùdo Siria, kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ. 6 Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ. 7 Nitorina ni nwọn dide, nwọn si salọ ni afẹ̀mọjumọ, nwọn si fi agọ wọn silẹ, ati ẹṣin wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ani, ibùdo wọn gẹgẹ bi o ti wà, nwọn si salọ fun ẹmi wọn. 8 Nigbati adẹtẹ̀ wọnyi de apa ikangun bùdo, nwọn wọ inu agọ kan lọ, nwọn jẹ, nwọn si mu, nwọn sì kó fadakà ati wura ati agbáda lati ibẹ lọ, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́; nwọn si tún pada wá, nwọn si wọ̀ inu agọ miran lọ, nwọn si kó lati ibẹ lọ pẹlu, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́. 9 Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba. 10 Bẹ̃ni nwọn wá, nwọn si ke si awọn onibodè ilu; nwọn si wi fun wọn pe, Awa de bùdo awọn ara Siria, si kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ, bẹ̃ni kò si ohùn enia kan, bikòṣe ẹṣin ti a so, ati kẹtẹkẹtẹ ti a so, ati agọ bi nwọn ti wà. 11 Ẹnikan si pè awọn onibodè; nwọn si sọ ninu ile ọba. 12 Ọba si dide li oru, o si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Emi o fi hàn nyin nisisiyi eyiti awọn ara Siria ti ṣe si wa. Nwọn mọ̀ pe, ebi npa wa; nitorina nwọn jade lọ ni bùdo lati fi ara wọn pamọ́ ni igbẹ wipe, Nigbati nwọn ba jade ni ilu, awa o mu wọn lãyè, awa o si wọ̀ inu ilu lọ. 13 Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si dahùn o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o mu marun ninu ẹṣin ti o kù, ninu awọn ti o kù ni ilu, kiyesi i, nwọn sa dabi gbogbo ọ̀pọlọpọ Israeli ti o kù ninu rẹ̀; kiyesi i, ani bi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia Israeli ti a run, si jẹ ki a ranṣẹ lọ iwò. 14 Nitorina nwọn mu ẹṣin kẹkẹ́ meji; ọba si ranṣẹ tọ̀ ogun awọn ara Siria lẹhin, wipe, Ẹ lọ iwò. 15 Nwọn si tọ̀ wọn lẹhin de Jordani: si wò o, gbogbo ọ̀na kún fun agbáda ati ohun elò ti awọn ara Siria gbé sọnù ni iyára wọn. Awọn onṣẹ si pada, nwọn si sọ fun ọba. 16 Awọn enia si jade lọ, nwọn si kó ibùdo awọn ara Siria. Bẹ̃ni a ntà oṣùwọn iyẹ̀fun kikunná kan ni ṣekeli kan, ati oṣuwọn barle meji ni ṣekeli kan, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. 17 Ọba si yàn ijòye na, lọwọ ẹniti o nfi ara tì, lati ṣe itọju ẹnu bodè: awọn enia si tẹ̀ ẹ mọlẹ ni bodè, o si kú, bi enia Ọlọrun na ti wi, ẹniti o sọ̀rọ nigbati ọba sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá. 18 O si ṣe, bi enia Ọlọrun na ti sọ fun ọba, wipe, Oṣùwọn barle meji fun ṣekeli kan, ati òṣuwọn iyẹfun kikunná kan, fun ṣekeli kan, yio wà ni iwòyi ọla ni ẹnu bodè Samaria: 19 Ijòye na si da enia Ọlọrun na li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, nisisiyi, bi Oluwa tilẹ ṣe ferese li ọrun, iru nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀. 20 Bẹ̃li o si ri fun u: nitori awọn enia tẹ̀ ẹ mọlẹ ni ẹnu bodè, o si kú.

2 Ọba 8

Obinrin Ará Ṣunemu náà Pada

1 ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje. 2 Obinrin na si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun na: on si lọ pẹlu ile rẹ̀, nwọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọdun meje. 3 O si ṣe lẹhin ọdun meje, ni obinrin na pada bọ̀ lati ilẹ awọn ara Filistia: on si jade lọ lati kepè ọba nitori ile rẹ̀ ati nitori ilẹ rẹ̀. 4 Ọba si mba Gehasi iranṣẹ enia Ọlọrun na sọ̀rọ, wipe, Mo bẹ̀ ọ, sọ gbogbo ohun nla, ti Eliṣa ti ṣe fun mi. 5 O si ṣe bi o ti nrò fun ọba bi o ti sọ okú kan di ãyè, si kiyesi i, obinrin na, ẹniti a sọ ọmọ rẹ̀ di ãyè kepè ọba nitori ilẹ rẹ ati nitori ile rẹ̀. Gehasi si wipe, Oluwa mi, ọba, eyi li obinrin na, eyi si li ọmọ rẹ̀ ti Eliṣa sọ di ãyè. 6 Nigbati ọba si bère lọwọ obinrin na, o rohin fun u. Ọba si yàn iwẹ̀fa kan fun u, wipe, Mu ohun gbogbo ti iṣe ti rẹ̀ pada fun u, ati gbogbo erè oko lati ọjọ ti o ti fi ilẹ silẹ titi di isisiyi. 7 Eliṣa si wá si Damasku; Benhadadi ọba Siria si nṣe aisàn; a si sọ fun u, wipe, Enia Ọlọrun de ihinyi. 8 Ọba si wi fun Hasaeli pe, Mu ọrẹ lọwọ rẹ, si lọ ipade enia Ọlọrun na, ki o si bère lọwọ Oluwa lọdọ rẹ̀, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi? 9 Bẹ̃ni Hasaeli lọ ipade rẹ̀, o si mu ọrẹ li ọwọ rẹ̀, ani ninu gbogbo ohun rere Damasku, ogoji ẹrù ibakasiẹ, o si de, o si duro niwaju rẹ̀, o si wipe, Ọmọ rẹ Benhadadi ọba Siria rán mi si ọ, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi? 10 Eliṣa si wi fun u pe, Lọ, ki o si sọ fun u pe, Iwọ iba sàn nitõtọ: ṣugbọn Oluwa ti fi hàn mi pe, nitõtọ on o kú. 11 On si tẹ̀ oju rẹ̀ mọ ọ gidigidi, titi oju fi tì i; enia Ọlọrun na si sọkun. 12 Hasaeli si wipe, Ẽṣe ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahùn pe, Nitoriti mo mọ̀ ibi ti iwọ o ṣe si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi idà pa, iwọ o si fọ́ ọmọ wẹwẹ́ wọn tútu, iwọ o si là inu awọn aboyun wọn. 13 Hasaeli si wipe, Ṣugbọn kinla? Iranṣẹ rẹ iṣe aja, ti yio fi ṣe nkan nla yi? Eliṣa si dahùn wipe, Oluwa ti fi hàn mi pe, iwọ o jọba lori Siria. 14 Bẹ̃li o lọ kuro lọdọ Eliṣa, o si de ọdọ oluwa rẹ̀; on si wi fun u pe, Kini Eliṣa sọ fun ọ? On si dahùn wipe, O sọ fun mi pe, Iwọ o sàn nitõtọ. 15 O si ṣe ni ijọ keji ni o mu aṣọ ti o nipọn, o kì i bọ̀ omi, o si tẹ́ ẹ le oju rẹ̀, bẹ̃li o kú. Hasaeli si jọba nipò rẹ̀.

Jehoramu Ọba Juda

16 Ati li ọdun karun Joramu, ọmọ Ahabu ọba Israeli, Jehoṣafati jẹ ọba Juda: nigbana Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. 17 Ẹni ọdun mejilelọgbọn li o jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu. 18 O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, bi ile Ahabu ti ṣe: nitori ọmọbinrin Ahabu li o nṣe aya rẹ̀; on si ṣe ibi niwaju Oluwa. 19 Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa Juda run, nitori Dafidi iranṣẹ rẹ̀, bi o ti ṣe ileri fun u, lati fun u ni imọlẹ ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọjọ gbogbo. 20 Li ọjọ rẹ̀ ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro li abẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn. 21 Bẹ̃ni Joramu rekọja siha Sairi, ati gbogbo awọn kẹkẹ́ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o yi i ka: ati awọn olori awọn kẹkẹ́: awọn enia si sá wọ inu agọ wọn. 22 Bẹ̃ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda titi o fi di oni yi. Nigbana ni Libna ṣọ̀tẹ li akokò kanna. 23 Iyokù iṣe Joramu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 24 Joramu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Ahasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ahasaya Ọba Juda

25 Li ọdun kejila Joramu ọmọ Ahabu ọba Israeli, Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. 26 Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Ataliah, ọmọbinrin Omri ọba Israeli. 27 O si rìn li ọ̀na ile Ahabu, o si ṣe ibi niwaju Oluwa, bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o nṣe ana ile Ahabu. 28 On si lọ pẹlu Joramu ọmọ Ahabu si ogun na ti o mba Hasaeli ọba Siria jà ni Ramoti-Gileadi; awọn ara Siria si ṣa Joramu li ọgbẹ́. 29 Joramu ọba si pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ti ṣa a ni Rama, nigbati o mba Hasaeli ọba Siria ja. Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu ọmọ Ahabu ni Jesreeli nitoriti o nṣe aisàn.

2 Ọba 9

A fi Òróró Yan Jehu ní Ọba Israẹli

1 ELIṢA woli si pè ọkan ninu awọn ọmọ woli, o si wi fun u pe, Dì amurè ẹ̀gbẹ rẹ, ki o si mu igò ororo yi lọwọ rẹ, ki o si lọ si Ramoti-Gileadi: 2 Nigbati iwọ ba si de ibẹ, ki iwọ ki o wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi li awari nibẹ, ki o si wọle, ki o si mu u ki o dide kuro lãrin awọn arakunrin rẹ̀, ki o si mu u lọ si yàra inu ile lọhun; 3 Ki o si mu igò ororo na, ki o si tú u si ori rẹ̀, ki o si wipe, Bayi li Oluwa wipe, Emi fi ororo yàn ọ li ọba li ori Israeli. Si ṣi ilẹkun, ki o si sá, má si ṣe duro. 4 Bẹ̃ni ọdọmọkunrin na, ani ọdọmọkunrin woli na, lọ si Ramoti-Gileadi. 5 Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun. 6 On si dide, o si wọ̀ inu ile: o si tú ororo na si i li ori, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia Oluwa, lori Israeli. 7 Iwọ o si kọlù ile Ahabu oluwa rẹ, ki emi o le gbẹsan ẹjẹ awọn woli iranṣẹ mi, ati ẹ̀jẹ gbogbo awọn iranṣẹ Oluwa lọwọ Jesebeli. 8 Nitori gbogbo ile Ahabu ni yio ṣegbé: emi o si ké gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Ahabu ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli: 9 Emi o si ṣe ile Ahabu bi ile Jeroboamu ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa ọmọ Ahijah; 10 Awọn aja yio si jẹ Jesebeli ni oko Jesreeli, kì yio si ẹniti yio sinkú rẹ̀. O si ṣi ilẹkùn, o si sá lọ. 11 Nigbana ni Jehu jade tọ̀ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀: ẹnikan si wi fun u pe, Alafia kọ́? nitori kini aṣiwère yi ṣe tọ̀ ọ wá? On si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ọkunrin na ati ọ̀rọ rẹ̀. 12 Nwọn si wipe, Eke; sọ fun wa wayi. On si wipe, Bayi bayi li o sọ fun mi wipe, Bayi ni Oluwa wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori Israeli. 13 Nigbana ni nwọn yára, olukulùku si mu agbáda rẹ̀, o si fi i si abẹ rẹ̀ lori atẹ̀gun, nwọn si fun ipè wipe, Jehu jọba.

Wọ́n pa Joramu, Ọba Israẹli

14 Bẹ̃ni Jehu ọmọ Jehoṣafati ọmọ Nimṣi ṣotẹ si Joramu. (Njẹ Joramu ti nṣọ Ramoti-Gileadi, on, ati gbogbo Israeli, nitoriti Hasaeli ọba Siria: 15 Ṣugbọn Joramu ọba ti pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ṣa a, nigbati o ba Hasaeli ọba Siria jà.) Jehu si wipe, Bi o ba ṣe ifẹ inu nyin ni, ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ki o jade lọ, tabi ki o yọ́ lọ kuro ni ilu lati lọ isọ ni Jesreeli. 16 Bẹ̃ni Jehu gùn kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli; nitori Joramu dùbulẹ nibẹ. Ahasiah ọba Juda si sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu. 17 Olùṣọ kan si duro ni ile iṣọ ni Jesreeli, o si ri ẹgbẹ́ Jehu bi o ti mbọ̀ wá, o si wipe, Mo ri ẹgbẹ́ kan. Joramu si wipe, Mu ẹlẹṣin kan, ki o si ranṣẹ lọ ipade wọn, ki o si wipe, Alafia kọ́? 18 Ẹnikan si lọ lori ẹṣin lati pade rẹ̀, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ pe, Iranṣẹ na de ọdọ wọn, ṣugbọn kò si tun pada wá mọ. 19 O si rán ekeji jade lori ẹṣin on si tọ̀ wọn wá, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si dahùn wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. 20 Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan. 21 Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli. 22 O si ṣe, nigbati Joramu ri Jehu li o wipe, Jehu, Alafia kọ́? On si wipe, Alafia kini, niwọ̀nbi iwà-agbère Jesebeli ìya rẹ ati iṣe ajẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tobẹ̃? 23 Joramu si yi ọwọ rẹ̀ pada, o si sá, o si wi fun Ahasiah pe, Ọtẹ̀ de, Ahasiah. 24 Jehu si fi gbogbo agbara rẹ̀ fà ọrun o si ta Joramu lãrin apa rẹ̀ mejeji, ọfà na si gbà ọkàn rẹ̀ jade, o si dojubolẹ ninu kẹkẹ́ rẹ̀. 25 Nigbana ni Jehu sọ fun Bidkari balogun rẹ̀, pe, Gbe e ki o si sọ ọ si oko Naboti ara Jesreeli: sa ranti bi igbati temi tirẹ jumọ ngùn kẹkẹ́ lẹhin Ahabu baba rẹ̀, Oluwa ti sọ ọ̀rọ-ìmọ yi sori rẹ̀. 26 Nitõtọ li ana emi ti ri ẹ̀jẹ Naboti ati ẹ̀jẹ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, li Oluwa wi; emi o si san a fun ọ ni oko yi, li Oluwa wi. Njẹ nitorina, ẹ mu u, ki ẹ si sọ ọ sinu oko na gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

A Pa Ahasaya Ọba Juda

27 Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ. 28 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. 29 Li ọdun ikọkanla Joramu ọmọ Ahabu ni Ahasiah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda.

A pa Jesebẹli Ayaba

30 Nigbati Jehu si de Jesreeli, Jesebeli gbọ́; on si le tìrõ, o si ta ori rẹ̀, o si yọju wode ni fèrese. 31 Bi Jehu si ti ngbà ẹnu-ọ̀na wọle, o wipe, Simri ti o pa oluwa rẹ̀ ri alafia bi? 32 On si gbé oju rẹ̀ si òke fèrese, o si wipe, Tani nṣe ti emi? tani? Awọn iwẹ̀fa meji bi mẹta si yọju si i lode. 33 On si wipe, Ẹ tari rẹ̀ silẹ. Nwọn si tari rẹ̀ silẹ: diẹ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ si ta si ara ogiri, ati si ara awọn ẹṣin: on si tẹ̀ ẹ mọlẹ. 34 Nigbati o si wọle, o jẹ, o si mu, o si wipe, Ẹ lọ iwò obinrin egun yi wàyi, ki ẹ si sìn i: nitori ọmọbinrin ọba li on iṣe. 35 Nwọn si lọ isin i; ṣugbọn nwọn kó ri ninu rẹ̀ jù agbari, ati ẹsẹ̀ ati atẹ́lẹwọ rẹ̀ lọ. 36 Nitorina nwọn si tun pada wá, nwọn si sọ fun u. On si wipe, Eyi li ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀ ara Tiṣbi wipe, Ni oko Jesreeli li awọn aja yio jẹ ẹran-ara Jesebeli: 37 Okú Jesebeli yio si dàbi imí ni igbẹ́, ni oko Jesreeli; tobẹ̃ ti nwọn kì yio wipe, Jesebeli li eyi.

2 Ọba 10

A pa Àwọn Ọmọ Ọba Ahabu

1 AHABU si ni ãdọrin ọmọ ọkunrin ni Samaria. Jehu si kọwe, o si ranṣẹ si Samaria si awọn olori Jesreeli, si awọn àgbagba, ati si awọn ti ntọ́ awọn ọmọ Ahabu, wipe, 2 Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba ti de ọdọ nyin, bi o ti jẹpe, awọn ọmọ oluwa nyin mbẹ lọdọ nyin, ati kẹkẹ́ ati ẹṣin mbẹ lọdọ nyin, ilu olodi pẹlu ati ihamọra. 3 Ki ẹ wò ẹniti o sàn jùlọ ati ti o si yẹ jùlọ ninu awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ gbé e ka ori-itẹ́ baba rẹ̀, ki ẹ si jà fun ile oluwa nyin. 4 Ṣugbọn ẹ̀ru bà wọn gidigidi, nwọn si wipe, Kiyesi i, ọba meji kò duro niwaju rẹ̀: awa o ha ti ṣe le duro? 5 Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ. 6 Nigbana ni o kọ iwe lẹrinkeji si wọn wipe, Bi ẹnyin ba ṣe ti emi, bi ẹnyin o si fi eti si ohùn mi, ẹ mu ori awọn ọkunrin na, awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá ni Jesreeli ni iwòyi ọla. Njẹ awọn ọmọ ọba, ãdọrin ọkunrin, mbẹ pẹlu awọn enia nla ilu na ti ntọ́ wọn. 7 O si ṣe, nigbati iwe na de ọdọ wọn, ni nwọn mu awọn ọmọ ọba, nwọn si pa ãdọrin ọkunrin, nwọn si kó ori wọn sinu agbọ̀n, nwọn si fi wọn ranṣẹ si i ni Jesreeli. 8 Onṣẹ kan si de, o si sọ fun u, wipe, nwọn ti mu ori awọn ọmọ ọba wá. On si wipe, Ẹ tò wọn li okiti meji ni atiwọ̀ ẹnu bodè, titi di owurọ̀. 9 O si ṣe li owurọ̀, o si jade lọ, o si duro, o si wi fun gbogbo awọn enia pe, Olododo li ẹnyin: kiyesi i, emi ṣọ̀tẹ si oluwa mi, mo si pa a: ṣugbọn tani pa gbogbo awọn wọnyi? 10 Njẹ ẹ mọ̀ pe, kò si ohunkan ninu ọ̀rọ Oluwa, ti Oluwa sọ niti ile Ahabu ti yio bọ́ silẹ, nitori ti Oluwa ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀. 11 Bẹ̃ni Jehu pa gbogbo awọn ti o kù ni ile Ahabu ni Jesreeli ati gbogbo awọn enia nla rẹ̀, ati awọn ibatan rẹ̀, ati awọn alufa rẹ̀, titi on kò fi kù ọkan silẹ fun u.

A Pa Àwọn Ìbátan Ahasaya Ọba

12 On si dide, o si mbọ̀ o si wá si Samaria: bi o si ti wà nibi ile irẹ́run agutan li oju ọ̀na. 13 Jehu pade awọn arakunrin Ahasiah ọba Juda, o si wipe, Tali ẹnyin? Nwọn si dahùn wipe, Awa arakunrin Ahasiah ni; awa si nsọ̀kalẹ lati lọ ikí awọn ọmọ ọba ati awọn ọmọ ayaba. 14 On si wipe, Ẹ mu wọn lãyè, nwọn si mu wọn lãyè, nwọn si pa wọn nibi iho ile irẹ́run agùtan, ani ọkunrin mejilelogoji, bẹ̃ni kò si kù ẹnikan wọn.

A Pa Àwọn Ìbátan Ahabu yòókù

15 Nigbati o si jade nibẹ, o ri Jehonadabu ọmọ Rekabu mbọ̀wá ipade rẹ̀; o si sure fun u, o si wi fun u pe, Ọkàn rẹ ha ṣe dede bi ọkàn mi ti ri si ọkàn rẹ? Jehonadabu si dahùn wipe, Bẹ̃ni. Bi bẹ̃ni, njẹ fun mi li ọwọ rẹ. O si fun u li ọwọ rẹ̀; on si fà a sọdọ rẹ̀ sinu kẹkẹ́. 16 On si wipe, Ba mi lọ ki o si wò itara mi fun Oluwa. Bẹ̃ni nwọn mu u gùn kẹkẹ́ rẹ̀. 17 Nigbati o si de Samaria, o pa gbogbo awọn ti o kù fun Ahabu ni Samaria, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ fun Elijah.

A Pa Àwọn Abọ̀rìṣà Baali

18 Jehu si kó gbogbo awọn enia jọ, o si wi fun wọn pe, Ahabu sìn Baali diẹ, ṣugbọn Jehu yio sìn i pupọ. 19 Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run. 20 Jehu si wipe, Ẹ yà apejọ si mimọ́ fun Baali; nwọn si kede rẹ̀. 21 Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji. 22 On si wi fun ẹniti o wà lori yará babaloriṣa pe, Kó aṣọ wá fun gbogbo awọn olùsin Baali. On si kó aṣọ jade fun wọn wá. 23 Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali. 24 Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀. 25 O si ṣe, bi a si ti pari ati ru ẹbọ sisun, ni Jehu wi fun awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun pe, Wọle, ki ẹ si pa wọn; ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o jade. Nwọn si fi oju idà pa wọn; awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun si gbé wọn sọ si ode, nwọn si wọ̀ inu odi ile Baali. 26 Nwọn si kó awọn ere lati ile Baali jade, nwọn si sun wọn. 27 Nwọn si wo ere Baali lulẹ, nwọn si wo ile Baali lulẹ, nwọn si ṣe e ni ile igbẹ́ titi di oni yi. 28 Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israeli. 29 Ṣugbọn Jehu kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o mu Israeli ṣẹ̀, eyinì ni, awọn ẹgbọ̀rọ malu wura ti o wà ni Beteli, ati eyiti o wà ni Dani. 30 Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli. 31 Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀.

Ikú Jehu

32 Li ọjọ wọnni Oluwa bẹ̀rẹ si iké Israeli kuru: Hasaeli si kọlù wọn ni gbogbo agbègbe Israeli; 33 Lati Jordani nihà ilà-õrùn, gbogbo ilẹ Gileadi, awọn enia Gadi, ati awọn enia Reubeni, ati awọn enia Manasse, lati Aroeri, ti o wà leti odò Arnoni, ani Gileadi ati Baṣani. 34 Ati iyokù iṣe Jehu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati gbogbo agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 35 Jehu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: nwọn si sìn i ni Samaria. Jehoahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. 36 Ọjọ ti Jehu jọba lori Israeli ni Samaria sì jẹ ọdun mejidilọgbọ̀n.

2 Ọba 11

Atalaya Ayaba Juda

1 NIGBATI Ataliah iyá Ahasiah si ri pe ọmọ on kú, o dide, o si pa gbogbo iru-ọmọ ọba run. 2 Ṣugbọn Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasiah, mu Joaṣi ọmọ Ahasiah, o si ji i gbé kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa; nwọn si pa a mọ́ ninu iyẹ̀wu kuro lọdọ Ataliah, on, ati alagbatọ́ rẹ̀, ti a kò si fi pa a. 3 A si pa a mọ́ pẹlu rẹ̀ ni ile Oluwa li ọdun mẹfa. Ataliah si jọba lori ilẹ na. 4 Li ọdun keje Jehoiada si ranṣẹ o si mu awọn olori lori ọ̀rọrún, pẹlu awọn balogun, ati awọn olùṣọ, o si mu wọn wá si ọdọ rẹ̀ sinu ile Oluwa, o si ba wọn da majẹmu, o si mu wọn bura ni ile Oluwa, o si fi ọmọ ọba hàn wọn. 5 O si paṣẹ fun wọn wipe, Eyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin ti nwọle li ọjọ isimi, yio ṣe olùtọju iṣọ ile ọba; 6 Idamẹta yio si wà li ẹnu ọ̀na Suri; idamẹta yio si wà li ẹnu-ọ̀na lẹhin ẹ̀ṣọ: bẹ̃li ẹnyin o tọju iṣọ́ ile na, lati da abo bò o. 7 Ati idajì gbogbo ẹnyin ti njade lọ li ọjọ isimi, ani awọn ni yio tọju iṣọ ile Oluwa yi ọba ka. 8 Ẹnyin o si pa agbo yi ọba ka, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹniti o ba si wọ̀ arin ẹgbẹ́ ogun na, ki a pa a: ki ẹnyin ki o si wà pẹlu ọba bi o ti njade lọ, ati bi o ti mbọ̀wá ile. 9 Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa. 10 Alufa na si fi ọ̀kọ ati asà Dafidi ọba ti o wà ni ile Oluwa fun awọn olori ọ̀rọrún. 11 Awọn ẹ̀ṣọ si duro, olukulùku pẹlu ohun ijà rẹ̀ lọwọ rẹ̀ yi ọba ka, lati igun ọtún ile Oluwa, titi de igun osì ile Oluwa, nihà pẹpẹ ati ile Oluwa. 12 On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ. 13 Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn ẹ̀ṣọ ati ti awọn enia, o tọ̀ awọn enia na wá ninu ile Oluwa. 14 Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀! 15 Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa. 16 Nwọn si gbé ọwọ le e; on si gbà ọ̀na ti awọn ẹṣin ngbà wọ̀ ile ọba: nibẹ ni a si pa a.

Jehoiada Ṣe Àtúnṣe

17 Jehoiada si da majẹmu lãrin Oluwa ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o mã ṣe enia Oluwa; ati lãrin ọba pẹlu awọn enia. 18 Gbogbo enia ilẹ na si lọ sinu ile Baali, nwọn si wo o lulẹ: awọn pẹpẹ rẹ̀ ati awọn ere rẹ̀ ni nwọn fọ́ tútu patapata, nwọn si pa Mattani alufa Baali niwaju pẹpẹ na. Alufa na si yàn awọn olori si ile Oluwa. 19 On si mu awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, ati awọn ẹ̀ṣọ, ati gbogbo enia ilẹ na; nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá, nwọn si gbà oju ẹnu-ọ̀na ẹ̀ṣọ wọ̀ ile ọba. O si joko lori ìtẹ awọn ọba. 20 Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, ilu na si tòro; nwọn si fi idà pa Ataliah li eti ile ọba. 21 Ẹni ọdun meje ni Jehoaṣi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba.

2 Ọba 12

Joaṣi Ọba Juda

1 LI ọdun keje Jehu ni Jehoaṣi bẹ̀rẹ si ijọba; ogoji ọdun li o si jọba ni Jerusalemu. Orukọ iyà rẹ̀ a mã jẹ Sibiah ti Beerṣeba. 2 Jehoaṣi si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa li ọjọ rẹ̀ gbogbo ninu eyiti Jehoiada alufa nkọ́ ọ. 3 Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. 4 Jehoaṣi si wi fun awọn alufa pe, Gbogbo owo ti a yà si mimọ́ ti a si mu wá sinu ile Oluwa, ani olukuluku owo ti o kọja, ati owo idiyele olukuluku, ati gbogbo owo ti o ti inu ọkàn olukuluku wá lati mu wá sinu ile Oluwa. 5 Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya. 6 O si ṣe, li ọdun kẹtalelogun Jehoaṣi ọba, awọn alufa kò iti tun ẹya ile na ṣe. 7 Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na. 8 Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe. 9 Ṣugbọn Jehoiada alufa mu apoti kan, o si dá ideri rẹ̀ lu, o si fi i si ẹba pẹpẹ na, li apa ọtún bi ẹnikan ti nwọ̀ inu ile Oluwa lọ: awọn alufa ti o si ntọju iloro na fi gbogbo owo ti a mu wá inu ile Oluwa sinu rẹ̀. 10 O si ṣe, nigbati nwọn ri pe, owo pupọ̀ mbẹ ninu apoti na, ni akọwe ọba, ati olori alufa gòke wá, nwọn si dì i sinu apò, nwọn si kà iye owo ti a ri ninu ile Oluwa. 11 Nwọn si fi owo na ti a kà le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, awọn ti o nṣe abojuto ile Oluwa: nwọn si ná a fun awọn gbẹnagbẹna, ati awọn akọle, ti nṣiṣẹ ile Oluwa. 12 Ati fun awọn ọmọle, ati awọn agbẹ́kuta, ati lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tun ẹya ile Oluwa ṣe, ati fun gbogbo eyi ti a ná fun ile na lati tun u ṣe. 13 Ṣugbọn ninu owo ti a mu wá sinu ile Oluwa, a kò fi ṣe ọpọ́n fadakà, alumagàji fitila, awokoto, ipè ohun èlo wura tabi ohun elò fadakà kan fun ile Oluwa: 14 Ṣugbọn nwọn fi i fun awọn ti nṣiṣe na, nwọn si fi tun ile Oluwa ṣe. 15 Nwọn kò si ba awọn ọkunrin na ṣirò, li ọwọ ẹniti nwọn fi owo na le, lati fi fun awọn ti nṣiṣẹ; nitoriti nwọn ṣe otitọ. 16 Owo ẹbọ irekọja ati owo ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni a kò mu wá sinu ile Oluwa: ti awọn alufa ni. 17 Nigbana ni Hasaeli ọba Siria gòke lọ, o si ba Gati jà, o si kó o: Hasaeli si doju rẹ̀ kọ ati gòke lọ si Jerusalemu. 18 Jehoaṣi ọba Juda si mu gbogbo ohun èlo mimọ́ ti Jehoṣafati, ati Jehoramu, ati Ahasiah awọn baba rẹ̀, awọn ọba Juda ti yà si mimọ́, ati ohun mimọ́ tirẹ̀, ati gbogbo wura ti a ri nibi iṣura ile Oluwa, ati ni ile ọba, o si rán a si Hasaeli ọba Siria: on si lọ kuro ni Jerusalemu. 19 Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 20 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si dide, nwọn si dì rikiṣi, nwọn si pa Joaṣi ni ile Millo, ti o sọ̀kalẹ lọ si Silla. 21 Nitori Josakari ọmọ Simeati ati Jehosabadi ọmọ Ṣomeri, awọn iranṣẹ rẹ̀ pa a, o si kú; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 13

Jehoahasi Ọba Israẹli

1 LI ọdun kẹtalelogun Joaṣi ọmọ Ahasiah ọba Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria. 2 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, o si tẹ̀le ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: on kò si lọ kuro ninu rẹ̀. 3 Ibinu Oluwa si rú si Israeli, o si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, li ọjọ wọn gbogbo. 4 Jehoahasi si bẹ̀ Oluwa, Oluwa si gbọ́ tirẹ̀; nitoriti o ri inira Israeli, nitoriti ọba Siria ni wọn lara. 5 Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ. 6 Ṣugbọn nwọn kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ṣugbọn nwọn rìn ninu rẹ̀: ere-oriṣa si wà ni Samaria pẹlu. 7 Bẹ̃ni kò kù ninu awọn enia fun Jehoahasi, bikòṣe ãdọta ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́ mẹwa, ati ẹgbãrin ẹlẹsẹ̀; nitoriti ọba Siria ti pa wọn run, o si ti lọ̀ wọn mọlẹ bi ẽkuru. 8 Ati iyokù iṣe Jehoahasi, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. 9 Jehoahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i ni Samaria: Joaṣi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Jehoaṣi Ọba Israẹli

10 Li ọdun kẹtadilogoji Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ọdun mẹrindilogun. 11 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa; on kò lọ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: ṣugbọn o rìn ninu wọn. 12 Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi ba Amasiah ọba Juda jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 13 Joaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Jeroboamu si joko lori itẹ́ rẹ̀: a si sìn Joaṣi ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli.

Ikú Eliṣa

14 Eliṣa si ṣe aisàn ninu eyi ti kò ni yè, Joaṣi ọba Israeli si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, o si sọkun si i li oju, o si wipe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀! 15 Eliṣa si wi fun u pe, Mu ọrun pẹlu ọfà: on si mu ọrun ati ọfà. 16 O si wi fun ọba Israeli pe, Fi ọwọ rẹ le ọrun na: on si fi ọwọ rẹ̀ le e: Eliṣa si fi ọwọ tirẹ̀ le ọwọ ọba. 17 O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn. 18 O si wipe, Kó awọn ọfà na. O si kó wọn. O si wi fun ọba Israeli pe, Ta si ilẹ. On si ta lẹrinmẹta, o si mu ọwọ duro. 19 Enia Ọlọrun na si binu si i, o si wipe, Iwọ iba ta lẹrinmarun tabi mẹfa; nigbana ni iwọ iba kọlù Siria titi iwọ iba fi run u: ṣugbọn nisisiyi iwọ o kọlù Siria nigbà mẹta. 20 Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun. 21 O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.

Ogun Láàrin Israẹli ati Siria

22 Ṣugbọn Hasaeli ọba Siria ni Israeli lara ni gbogbo ọjọ Jehoahasi. 23 Oluwa si ṣe oju rere si wọn, o si ṣãnu fun wọn, o si ṣe akiyesi wọn, nitoriti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, kò si fẹ run wọn, bẹ̃ni kò si ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀ titi di isisiyi. 24 Bẹ̃ni Hasaeli ọba Siria kú; Benhadadi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. 25 Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi si tun gbà ilu wọnni pada lọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, ti o ti fi ogun gbà lọwọ Jehoahasi baba rẹ̀. Igba mẹta ni Joaṣi ṣẹgun rẹ̀, o si gbà awọn ilu Israeli pada.

2 Ọba 14

Amasaya Ọba Juda

1 LI ọdun keji Joaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli ni Amasiah ọmọ Joaṣi jọba lori Juda. 2 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Jehoadani ti Jerusalemu. 3 On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi Dafidi baba rẹ̀: o ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti Joaṣi baba rẹ̀ ti ṣe. 4 Kiki a kò mu ibi giga wọnni kuro; sibẹ awọn enia nṣe irubọ, nwọn si nsun turari ni ibi giga wọnni. 5 O si ṣe bi ijọba na ti fi idi mulẹ lọwọ rẹ̀ ni o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o ti pa ọba baba rẹ̀. 6 Ṣugbọn awọn ọmọ awọn apania na ni kò pa: gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu iwe ofin Mose ninu eyiti Oluwa paṣẹ wipe, A kò gbọdọ pa baba fun ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa ọmọ fun baba; ṣugbọn olukuluku li a o pa fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 7 On pa ẹgbãrun ninu awọn ara Edomu ni afonifojì iyọ, o si fi ogun kó Sela, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jokteeli titi di oni yi. 8 Nigbana ni Amasiah rán ikọ̀ si Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israeli wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju. 9 Jehoaṣi ọba Israeli si ranṣẹ si Amasiah ọba Juda, pe, Igi ẹgún ti mbẹ ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti mbẹ ni Lebanoni pe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ ọkunrin mi li aya: ẹranko igbẹ́ kan ti mbẹ ni Lebanoni kọja lọ, o si tẹ̀ igi ẹ̀gun na mọlẹ. 10 Iwọ ti ṣẹgun Edomu nitõtọ, ọkàn rẹ si gbé ọ soke: mã ṣogo, ki o si gbe ile rẹ: nitori kini iwọ ṣe nfiràn si ifarapa rẹ, ki iwọ ki o lè ṣubu, iwọ, ati Juda pẹlu rẹ? 11 Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda. 12 A si le Juda niwaju Israeli; nwọn si sá olukuluku sinu agọ rẹ̀. 13 Jehoaṣi ọba Israeli si mu Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi ọmọ Ahasiah ni Betṣemeṣi, o si wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu palẹ lati ẹnu bodè Efraimu titi de ẹnu bodè igun, irinwo igbọnwọ. 14 O si kó gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun èlo ti a ri ninu ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, ati ògo, o si pada si Samaria. 15 Ati iyokù iṣe Jehoaṣi ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, ati bi o ti ba Amasiah ọba Judah jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 16 Jehoaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli; Jeroboamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ikú Amasaya Ọba Juda

17 Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda wà li ọdun mẹ̃dogun lẹhin ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli. 18 Ati iyokù iṣe Amasiah, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 19 Nwọn si dì rikiṣi si i ni Jerusalemu: o si salọ si Lakiṣi; ṣugbọn nwọn ranṣẹ tọ̀ ọ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ. 20 Nwọn si gbé e wá lori ẹṣin: a si sin i ni Jerusalemu pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. 21 Gbogbo awọn enia Juda si mu Asariah ẹni ọdun mẹrindilogun, nwọn si fi i jọba ni ipò Amasiah baba rẹ̀. 22 On si kọ́ Elati, o si mu u pada fun Juda, lẹhin ti ọba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀.

Jeroboamu Keji, Ọba Israẹli

23 Li ọdun kẹ̃dogun Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, o si jọba li ọdun mọkanlelogoji. 24 O si ṣe buburu li oju Oluwa: kò yà kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀. 25 O si tun mu agbègbe ilẹ Israeli pada lati atiwọ̀ Hamati titi de okun pẹ̀tẹlẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti sọ nipa ọwọ iranṣẹ rẹ̀ Jona woli, ọmọ Amittai, ti Gat-heferi. 26 Nitori Oluwa ri ipọnju Israeli pe, o korò gidigidi: nitori kò si ọmọ-ọdọ, tabi omnira tabi olurànlọwọ kan fun Israeli. 27 Oluwa kò si wipe on o pa orukọ Israeli rẹ́ labẹ ọrun: ṣugbọn o gbà wọn nipa ọwọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi. 28 Ati iyokù iṣe Jeroboamu ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, bi o ti jagun si, ati bi o ti gbà Damasku, ati Hamati, ti iṣe ti Juda, pada fun Israeli, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 29 Jeroboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ani, pẹlu awọn ọba Israeli; Sakariah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 15

Asaraya Ọba Juda

1 LI ọdun kẹtadilọgbọ̀n Jeroboamu ọba Israeli ni Asariah (Ussiah) ọmọ Amasiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. 2 Ẹni ọdun mẹrindilogun li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a ma jẹ Jekoliah ti Jerusalemu. 3 O si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe; 4 Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. 5 Oluwa si kọlù ọba na, bẹ̃li o di adẹtẹ̀ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile ihámọ: Jotamu ọmọ ọba si wà lori ile na, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na. 6 Ati iyokù iṣe Asariah, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 7 Asariah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀, ni ilu Dafidi: Jotamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Sakaraya Ọba Israẹli

8 Li ọdun kejidilogoji Asariah ọba Juda ni Sakariah ọmọ Jeroboamu jọba lori Israeli ni Samaria li oṣù mẹfa. 9 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi awọn baba rẹ̀ ti ṣe: on kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀. 10 Ṣallumu ọmọ Jabeṣi si dì rikiṣi si i, o si kọlù u niwaju awọn enia, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀. 11 Ati iyokù iṣe Sakariah, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. 12 Eyi li ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun Jehu wipe, Awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli, bẹ̃li o si ri.

Ṣalumu Ọba Israẹli

13 Ṣallumu ọmọ Jabeṣi bẹ̀rẹ si ijọba li ọdun kọkandilogoji Ussiah ọba Juda; o si jọba oṣù kan gbáko ni Samaria. 14 Nitoriti Menahemu ọmọ Gadi gòke lati Tirsa lọ, o si wá si Samaria, o si kọlù Ṣallumi ọmọ Jabeṣi ni Samaria, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀. 15 Ati iyokù iṣe Ṣallumu, ati rikiṣi rẹ̀ ti o dì, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. 16 Nigbana ni Menahemu kọlù Tifsa, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ agbègbe rẹ̀ wọnni lati Tifsa lọ: nitoriti nwọn kò ṣi i silẹ fun u, nitorina li o ṣe kọlù u; ati gbogbo awọn obinrin aboyun inu rẹ̀ li o là ni inu.

Menahemu Ọba Israẹli

17 Li ọdun kọkandilogoji Asariah ọba Juda ni Menahemu ọmọ Gadi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba ọdun mẹwa ni Samaria. 18 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, li ọjọ rẹ̀ gbogbo. 19 Fulu ọba Assiria si gbé ogun tì ilẹ na: Menahemu si fi ẹgbẹrin talenti fadakà fun Fulu, ki ọwọ rẹ̀ ki o le pẹlu on lati fi idi ijọba na mulẹ lọwọ rẹ̀. 20 Menahemu si fi agbara gbà owo na lọwọ Israeli, ani lọwọ gbogbo awọn ọlọrọ̀, ãdọta ṣekeli fadakà lọwọ olukuluku enia, lati fi fun ọba Assiria. Bẹ̃ni ọba Assiria yipada, kò si duro ni ilẹ na. 21 Ati iyokù iṣe Menahemu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? 22 Menahemu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Pekahiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Pekahaya, Ọba Israẹli

23 Ni ãdọta ọdun Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba ọdun meji. 24 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀. 25 Ṣugbọn Peka ọmọ Remaliah, olori-ogun rẹ̀, dì rikiṣi si i, o si kọlù u ni Samaria, li odi ile ọba, pẹlu Argobu, ati Arie, ati ãdọta enia ninu awọn ọmọ Gileadi pẹlu rẹ̀: o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀. 26 Ati iyokù iṣe Pekahiah, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

Peka Ọba Israẹli

27 Li ọdun kejilelãdọta Asariah ọba Juda ni Peka ọmọ Remaliah bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ogun ọdun. 28 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀. 29 Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria. 30 Hoṣea ọmọ Ela si dì rikiṣi si Peka ọmọ Remaliah, o si kọlù u, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀, li ogun ọdun Jotamu ọmọ Ussiah. 31 Ati iyokù iṣe Peka, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

Jotamu, Ọba Juda

32 Li ọdun keji Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli, ni Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. 33 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku. 34 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa: o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ussiah baba rẹ̀ ti ṣe. 35 Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. On kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa. 36 Ati iyokù iṣe Jotamu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 37 Li ọjọ wọnni Oluwa bẹ̀rẹ si irán Resini ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah si Juda. 38 Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀, Ahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 16

Ahasi, Ọba Juda

1 LI ọdun kẹtadilogun Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. 2 Ẹni ogún ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu, kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀. 3 Ṣugbọn o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, nitõtọ, o si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná pẹlu, gẹgẹ bi iṣe irira awọn keferi, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli. 4 O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori awọn òke kekeke, ati labẹ gbogbo igi tutu. 5 Nigbana ni Resini ọba Siria ati Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli gòke wá si Jerusalemu lati jagun: nwọn si do tì Ahasi, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀. 6 Li akokò na, Resini ọba Siria gbà Elati pada fun Siria, o si lé awọn enia Juda kuro ni Elati: awọn ara Siria si wá si Elati, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi. 7 Ahasi si rán onṣẹ si ọdọ Tiglat-pileseri ọba Assiria wipe, Iranṣẹ rẹ li emi, ati ọmọ rẹ; gòke wá, ki o si gbà mi lọwọ ọba Siria, ati lọwọ ọba Israeli, ti o dide si mi. 8 Ahasi si mu fadakà ati wura ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, o si rán a li ọrẹ si ọba Assiria. 9 Ọba Assiria si gbọ́ tirẹ̀: nitoriti ọba Assiria gòke wá si Damasku, o si kó o, o si mu u ni igbèkun lọ si Kiri, o si pa Resini. 10 Ahasi ọba si lọ si Damasku lati pade Tiglat-pileseri, ọba Assiria, o si ri pẹpẹ kan ti o wà ni Damasku: Ahasi ọba si rán awòran pẹpẹ na, ati apẹrẹ rẹ̀ si Urijah alufa, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ ọnà rẹ̀. 11 Urijah alufa si ṣe pẹpẹ kan gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba fi ranṣẹ si i lati Damasku wá; bẹ̃ni Urijah alufa ṣe e de atibọ̀ Ahasi ọba lati Damasku wá. 12 Nigbati ọba si ti Damasku de, ọba si ri pẹpẹ na: ọba si sunmọ pẹpẹ na, o si rubọ lori rẹ̀. 13 O si sun ẹbọ ọrẹ-sisun rẹ̀ ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, o si ta ohun-mimu rẹ̀ silẹ, o si wọ́n ẹ̀jẹ ọrẹ-alafia rẹ̀ si ara pẹpẹ na. 14 Ṣugbọn o mu pẹpẹ idẹ ti o wà niwaju Oluwa kuro lati iwaju ile na, lati agbedemeji pẹpẹ na, ati ile Oluwa, o si fi i si apa ariwa pẹpẹ na. 15 Ahasi ọba si paṣẹ fun Urijah alufa, wipe, Lori pẹpẹ nla ni ki o mã sun ọrẹ-sisun orowurọ̀ ati ọrẹ-jijẹ alalẹ, ati ẹbọ-sisun ti ọba, ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, pẹlu ọrẹ-sisun ti gbogbo awọn enia ilẹ na, ati ọrẹ-jijẹ wọn, ati ọrẹ ohun-mimu wọn; ki o si wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ ọrẹ-sisun na lori rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀jẹ ẹbọ miran: ṣugbọn niti pẹpẹ idẹ na emi o mã gbero ohun ti emi o fi i ṣe. 16 Bayi ni Urijah alufa ṣe, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba pa li aṣẹ. 17 Ahasi ọba si ké alafo ọnà arin awọn ijoko na, o si ṣi agbada na kuro lara wọn; o si gbé agbada-nla na kalẹ kuro lara awọn malu idẹ ti mbẹ labẹ rẹ̀, o si gbé e kà ilẹ ti a fi okuta tẹ́. 18 Ibi ãbò fun ọjọ isimi ti a kọ́ ninu ile na, ati ọ̀na ijade si ode ti ọba, ni o yipada kuro ni ile Oluwa nitori ọba Assiria. 19 Ati iyokù iṣe Ahasi ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 20 Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 17

Hoṣea Ọba Israẹli

1 LI ọdun kejila Ahasi ọba Juda ni Hoṣea ọmọ Ela bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, lori Israeli li ọdun mẹsan. 2 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi awọn ọba Israeli ti o ti wà ṣãju rẹ̀. 3 On ni Ṣalamaneseri ọba Assiria gòke tọ̀ wá; Hoṣea si di iranṣẹ rẹ̀, o si ta a li ọrẹ. 4 Ọba Assiria si ri ọ̀tẹ ninu Hoṣea: nitoriti o ti rán onṣẹ sọdọ So ọba Egipti, kò si mu ọrẹ fun ọba Assiria wá bi iti mã iṣe li ọdọdun; nitorina ni ọba Assiria há a mọ, o si dè e ni ile tubu. 5 Nigbana ni ọba Assiria gòke wá si gbogbo ilẹ na, o si gòke lọ si Samaria, o si dotì i li ọdun mẹta.

Ìṣubú Samaria

6 Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media. 7 O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran. 8 Ti nwọn si nrìn ninu ilana awọn keferi, ti Oluwa ti le jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, ati ti awọn ọba Israeli, ti nwọn ti ṣe. 9 Awọn ọmọ Israeli si ṣe ohun ikọ̀kọ ti kò tọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kọ́ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi. 10 Nwọn si gbé awọn ere kalẹ, nwọn si dá ere oriṣa si lori òke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo: 11 Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi ti Oluwa kó lọ niwaju wọn ti ṣe; nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu Oluwa soke. 12 Nitoriti nwọn sìn oriṣa wọnni, eyiti Oluwa ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣe nkan yi. 13 Sibẹ Oluwa jẹri si Israeli, ati si Juda, nipa ọwọ gbogbo awọn woli, ati gbogbo awọn ariran, wipe, Ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ́, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, ti mo rán si nyin nipa ọwọ awọn woli iranṣẹ mi. 14 Sibẹ nwọn kò fẹ igbọ́, ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, gẹgẹ bi ọrùn awọn baba wọn, ti kò gbà Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́. 15 Nwọn si kọ̀ ilana rẹ̀, ati majẹmu rẹ̀ silẹ, ti o ba awọn baba wọn dá, ati ẹri rẹ̀ ti o jẹ si wọn: nwọn si ntọ̀ ohun asan lẹhin, nwọn si huwa asan, nwọn si ntọ̀ awọn keferi lẹhin ti o yi wọn ka, niti ẹniti Oluwa ti kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe ṣe bi awọn. 16 Nwọn si kọ̀ gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, nwọn si ṣe ere didà fun ara wọn, ani, ẹgbọ̀rọ malu meji, nwọn si ṣe ere oriṣa, nwọn si mbọ gbogbo ogun ọrun, nwọn si sìn Baali. 17 Nwọn si mu ki awọn ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn ki o kọja lãrin iná, nwọn si nfọ̀ afọ̀ṣẹ, nwọn si nṣe alupayida, nwọn si tà ara wọn lati ṣe ibi niwaju Oluwa, lati mu u binu. 18 Nitorina ni Oluwa ṣe binu si Israeli gidigidi, o si mu wọn kuro niwaju rẹ̀: ọkan kò kù bikòṣe ẹ̀ya Juda nikanṣoṣo. 19 Juda pẹlu kò pa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wọn mọ́, ṣugbọn nwọn rìn ninu ilana Israeli ti nwọn ṣe. 20 Oluwa si kọ̀ gbogbo iru-ọmọ Israeli silẹ, o si wahala wọn, o si fi wọn le awọn akoni lọwọ, titi o si fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀. 21 Nitori ti o yà Israeli kuro ni idile Dafidi; nwọn si fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba: Jeroboamu si tì Israeli kuro lati má tọ̀ Oluwa lẹhin, o si mu wọn ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ nla. 22 Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀; nwọn kò lọ kuro ninu wọn; 23 Titi Oluwa fi mu Israeli kuro niwaju rẹ̀, bi o ti sọ nipa gbogbo awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a kó Israeli kuro ni ilẹ wọn lọ si Assiria, titi di oni yi.

Àwọn Ará Asiria Bẹ̀rẹ̀ sí Gbé Ilẹ̀ Israẹli

24 Ọba Assiria si kó enia lati Babeli wá, ati lati Kuta, ati lati Afa, ati lati Hamati, ati lati Sefarfaimi, o si fi wọn sinu ilu Samaria wọnni, ni ipò awọn ọmọ Israeli; nwọn si ni Samaria, nwọn si ngbe inu rẹ̀ wọnni. 25 O si ṣe li atètekọ-gbé ibẹ wọn, nwọn kò bẹ̀ru Oluwa: nitorina ni Oluwa ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, ti o pa ninu wọn. 26 Nitorina ni nwọn ṣe sọ fun ọba Assiria wipe, Awọn orilẹ-ède ti iwọ ṣi kuro, ti o si fi sinu ilu Samaria wọnni, kò mọ̀ iṣe Ọ̀lọrun ilẹ na: nitorina li on ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, si kiyesi i, nwọn pa wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ iṣe Ọlọrun ilẹ na. 27 Nigbana li ọba Assiria paṣẹ, wipe, Ẹ mu ọkan ninu awọn alufa ti ẹnyin ti kó ti ọhún wá lọ sibẹ; ẹ si jẹ ki wọn ki o lọ igbe ibẹ, ki ẹ si jẹ ki o ma kọ́ wọn ni iṣe Ọlọrun ilẹ na. 28 Nigbana ni ọkan ninu awọn alufa ti nwọn ti kó ti Samaria lọ, wá, o si joko ni Beteli, o si kọ́ wọn bi nwọn o ti mã bẹ̀ru Oluwa. 29 Ṣugbọn olukuluku orilẹ-ède ṣe oriṣa tirẹ̀, nwọn si fi wọn sinu ile ibi giga wọnni ti awọn ara Samaria ti ṣe, olukuluku orilẹ-ède ninu ilu ti nwọn ngbe. 30 Awọn enia Babeli ṣe agọ awọn wundia, ati awọn enia Kuti ṣe oriṣa Nergali, ati awọn enia Hamati ṣe ti Aṣima, 31 Ati awọn ara Afa ṣe ti Nibhasi ati ti Tartaki, ati awọn ara Sefarfaimu sun awọn ọmọ wọn ninu iná fun Adrammeleki ati Anammeleki awọn òriṣa Sefarfaimu. 32 Nwọn bẹ̀ru Oluwa pẹlu, nwọn si ṣe alufa ibi giga wọnni fun ara wọn, ninu awọn enia lasan, ti nrubọ fun wọn ni ile ibi giga wọnni. 33 Nwọn bẹ̀ru Oluwa, nwọn si nsìn oriṣa wọn gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède, ti nwọn kó lati ibẹ lọ. 34 Titi di oni yi nwọn nṣe bi iṣe wọn atijọ: nwọn kò bẹ̀ru Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò ṣe bi idasilẹ wọn, tabi ilàna wọn, tabi ofin ati aṣẹ ti Oluwa pa fun awọn ọmọ Jakobu, ti o sọ ni Israeli; 35 Awọn ẹniti Oluwa ti ba dá majẹmu, ti o si ti kilọ fun wọn, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ tẹ̀ ara nyin ba fun wọn, tabi ki ẹ sìn wọn, tabi ki ẹ rubọ si wọn: 36 Ṣugbọn Oluwa ti o mu nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, pẹlu agbara nla ati ninà apá, on ni ki ẹ mã bẹ̀ru, on ni ki ẹ si mã tẹriba fun, on ni ki ẹ sì mã rubọ si. 37 Ati idasilẹ wọnni, ati ilàna wọnni, ati ofin ati aṣẹ ti o ti kọ fun nyin, li ẹnyin o mã kiyesi lati mã ṣe li ọjọ gbogbo; ẹnyin kò si gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miràn. 38 Ati majẹmu ti mo ti ba nyin dá ni ẹnyin kò gbọdọ gbàgbe; bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran. 39 Ṣugbọn Oluwa Ọlọrun nyin ni ẹnyin o mã bẹ̀ru; on ni yio si gbà nyin lọwọ awọn ọta nyin gbogbo. 40 Nwọn kò si gbọ́, ṣugbọn nwọn ṣe bi iṣe wọn atijọ. 41 Bẹ̃li awọn orilẹ-ède wọnyi bẹ̀ru Oluwa, ṣugbọn nwọn tun sin awọn ere fifin wọn pẹlu; awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ-ọmọ wọn, bi awọn baba wọn ti ṣe, bẹ̃li awọn na nṣe titi fi di oni yi.

2 Ọba 18

Hesekaya, Ọba Juda

1 O si ṣe li ọdun kẹta Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli ni Hesekiah ọmọ Ahasi ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. 2 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Abi ọmọbinrin Sakariah. 3 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. 4 On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani. 5 O gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun Israeli; ati lẹhin rẹ̀ kò si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọba Juda, bẹ̃ni ṣãju rẹ̀ kò si ẹnikan. 6 Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose. 7 Oluwa si wà pẹlu rẹ̀; o si ṣe rere nibikibi ti o ba jade lọ: o si ṣọ̀tẹ si ọba Assiria, kò si sìn i mọ. 8 On kọlù awọn ara Filistia, ani titi de Gasa, ati agbègbe rẹ̀, lati ile iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi. 9 O si ṣe li ọdun kẹrin Hesekiah ọba, ti iṣe ọdun keje Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli, ni Ṣalmaneseri ọba Assiria gòke wá si Samaria, o si dotì i. 10 Lẹhin ọdun mẹta nwọn kó o; ani li ọdun kẹfa Hesekiah, eyini ni ọdun kẹsan Hoṣea ọba Israeli li a kó Samaria. 11 Ọba Assiria si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori leti odò Gosani, ati si ilẹ awọn ara Media wọnni: 12 Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.

Asiria Halẹ̀ Mọ́ Jerusalẹmu

13 Li ọdun kẹrinla Hesekiah ọba, ni Sennakeribu ọba Assiria gòke wá si gbogbo awọn ilu olodi Juda, o si kó wọn. 14 Hesekiah ọba Juda si ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wipe, Mo ti ṣẹ̀; padà lẹhin mi: eyiti iwọ ba bù fun mi li emi o rù. Ọba Assiria si bù ọ̃dunrun talenti fadakà, ati ọgbọ̀n talenti wura fun Hesekiah ọba Juda. 15 Hesekiah si fun u ni gbogbo fadakà ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba. 16 Li akòko na ni Hesekiah ké gbogbo wura kuro lara awọn ilẹ̀kun ile Oluwa, ati kuro lara ọwọ̀n wọnni ti Hesekiah ọba Juda ti fi wura bò, o si fi wọn fun ọba Assiria. 17 Ọba Assiria si rán Tartani, ati Rabsarisi, ati Rabṣake, lati Lakiṣi lọ si ọdọ Hesekiah ọba pẹlu ogun nla si Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn si de Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn de, nwọn si duro leti idari omi abàta òke, ti mbẹ li eti òpopo pápa afọṣọ. 18 Nigbati nwọn si ké si ọba, Eliakimu ọmọ Hilkiah ti iṣe olori ile na si jade tọ̀ wọn wá, ati Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu akọwe-iranti. 19 Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ sọ fun Hesekiah nisisiyi pe, Bayi ni ọba nla, ọba Assiria wi pe, Kini igbẹkẹle yi ti iwọ gbẹkẹle? 20 Iwọ wipe (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn), emi ni ìmọ ati agbara lati jagun. Njẹ tani iwọ gbẹkẹle, ti iwọ fi ṣọ̀tẹ si mi? 21 Kiyesi i, nisisiyi, iwọ gbẹkẹle ọ̀pa iyè fifọ yi, ani le Egipti, lara ẹniti bi ẹnikan ba fi ara tì, yio wọ̀ ọ li ọwọ lọ, yio si gun u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e. 22 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on ha kọ li ẹniti Hesekiah ti mu awọn ibi giga rẹ̀, ati awọn pẹpẹ rẹ̀ kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, Ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi ni Jerusalemu? 23 Njẹ nisisiyi, Mo bẹ̀ ọ, ba oluwa mi ọba Assiria ṣe adehun, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba lè ni enia to lati gùn wọn. 24 Njẹ bawo ni iwọ o ha ti ṣe le yi oju balogun kan ti o kere jùlọ pada ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si gbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́ ati fun ẹlẹṣin? 25 Emi ha dẹhin Oluwa gòke wá nisisiyi si ibi yi lati pa a run? Oluwa wi fun mi pe, Gòke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run. 26 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah, ati Ṣebna, ati Joa wi fun Rabṣake pe, Emi bẹ̀ ọ, ba awọn iranṣẹ rẹ sọ̀rọ li ède Siria; nitoriti awa gbọ́ ọ: ki o má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Juda li leti awọn enia ti mbẹ lori odi. 27 Ṣugbọn Rabṣake sọ fun wọn pe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ, ati si ọ, lati sọ ọ̀rọ wọnyi bi? kò ṣepe awọn ọkunrin ti o joko lori odi li o rán mi si, ki nwọn ki o le jẹ igbẹ́ ara wọn, ati ki nwọn ki o le mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin? 28 Nigbana ni Rabṣake duro, o si kigbe li ohùn rara li ède Juda o si sọ wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria: 29 Bayi li ọba wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori kì yio le gbà nyin kuro lọwọ rẹ̀: 30 Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a kì yio si fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ. 31 Ẹ máṣe fi eti si ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Fi ẹbùn wá oju rere mi, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá, ki olukuluku nyin ki o si mã jẹ ninu àjarà rẹ̀, ati olukuluku ninu igi ọ̀pọtọ rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si mu omi ninu àmu rẹ̀: 32 Titi emi o fi wá mu nyin kuro lọ si ilẹ bi ti ẹnyin tikara nyin, si ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọgbà ajara, ilẹ ororo olifi ati ti oyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ má ba kú: ki ẹ má si fi eti si ti Hesekiah, nigbati o ba ntàn nyin wipe, Oluwa yio gbà wa. 33 Ọkan ninu awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ti igbà ilẹ rẹ̀ kuro lọwọ ọba Assiria ri bi? 34 Nibo li awọn oriṣa Hamati, ati Arpadi gbe wà? Nibo li awọn oriṣa Sefarfaimu, Hena, ati Ifa gbe wà? Nwọn ha gbà Samaria kuro lọwọ mi bi? 35 Tani ninu gbogbo awọn oriṣa ilẹ wọnni ti o gbà ilẹ wọn kuro lọwọ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro lọwọ mi? 36 Ṣugbọn awọn enia pa ẹnu wọn mọ́, nwọn kò si da a li ohun ọ̀rọ kan: nitori aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a li ohùn. 37 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah ti iṣe olori ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu akọwe-iranti wá sọdọ Hesekiah, ti awọn, ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.

2 Ọba 19

Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn Lọ́wọ́ Aisaya

1 O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bò ara rẹ̀, o si lọ sinu ile Oluwa. 2 O si rán Eliakimu, ti iṣe olori ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn àgba alufa, ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bò ara, sọdọ Isaiah woli ọmọ Amosi. 3 Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Ọjọ oni ọjọ wàhala ni, ati ti ibawi, ati ẹgàn: nitoriti awọn ọmọ de oju-ibí, kò si si agbara lati bi. 4 Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Rabṣake ẹniti ọba Assiria oluwa rẹ̀ ti rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè, yio si ba a wi nitori ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́: njẹ nitorina, gbé adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù. 5 Bẹ̃li awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah. 6 Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ sọ fun oluwa nyin, Bayi li Oluwa wi pe, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọnni, ti o ti gbọ́, ti awọn iranṣẹ ọba Assiria fi sọ ọ̀rọ odi si mi. 7 Kiyesi i, emi o rán ẽmi kan si i, on o si gbọ́ ariwo, yio si pada si ilẹ on tikalarẹ̀; emi o si mu u ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.

Àwọn ará Asiria tún ranṣẹ ìhàlẹ̀ mìíràn

8 Bẹ̃ni Rabṣake pada, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitoriti o ti gbọ́ pe o ti lọ kuro ni Lakiṣi. 9 Nigbati o si gburo Tirhaka ọba Etiopia, pe, Kiyesi i, o jade wá lati ba ọ jagun; o si tun rán awọn onṣẹ si ọdọ Hesekiah wipe, 10 Bayi li ẹnyin o sọ fun Hesekiah ọba Juda, wipe, Máṣe jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọwọ ọba Assiria. 11 Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si gbogbo ilẹ, ni pipa wọn run patapata: a o ha si gbà iwọ bi? 12 Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun; bi Gosani, ati Harani, ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti o wà ni Telassari? 13 Nibo li ọba Hamati, ati ọba Arpadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wà? 14 Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn onṣẹ na, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ sinu ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa. 15 Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye. 16 Dẹti rẹ silẹ Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: ki o si gbọ́ ọ̀rọ Sennakeribu ti o rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè. 17 Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti pa awọn orilẹ-ède run ati ilẹ wọn. 18 Nwọn si ti gbe òriṣa wọn sọ sinu iná; nitoriti nwọn kì iṣe ọlọrun, bikòṣe iṣẹ ọwọ enia, igi ati okuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run. 19 Njẹ nitorina, Oluwa Ọlọrun wa, emi mbẹ̀ ọ, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ilẹ ọba aiye le mọ̀ pe iwọ Oluwa iwọ nikanṣoṣo ni Ọlọrun.

Iṣẹ́ Tí Aisaya Rán sí Ọba

20 Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, adura ti iwọ ti gbà si mi si Sennakeribu ọba Assiria emi ti gbọ́. 21 Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀; Wundia ọmọbinrin Sioni ti kẹgàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ. 22 Tani iwọ sọ̀rọ buburu si ti iwọ si kẹgàn? ati tani iwọ gbé ohùn rẹ si òke si, ti iwọ gbé oju rẹ ga si òke? ani si Ẹni-Mimọ Israeli. 23 Nipa awọn onṣẹ rẹ, iwọ ti sọ̀rọ buburu si Oluwa, ti nwọn si wipe, Ọpọlọpọ kẹkẹ́ mi li emi fi de ori awọn òke-nla, si ori Lebanoni, emi o si ké igi kedari giga rẹ̀ lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀; emi o si lọ si ori òke ibùwọ rẹ̀, sinu igbó Karmeli rẹ̀. 24 Emi ti wà kànga, emi si ti mu ajèji omi, atẹlẹsẹ̀ mi li emi si ti fi gbẹ gbogbo odò Egipti. 25 Iwọ kò ti gbọ́, lailai ri emi ti ṣe e, nigba atijọ emi si ti mura tẹlẹ nisisiyi emi ti mu u ṣẹ, ki iwọ ki o le mã sọ ilu olodi wọnni di ahoro, ani di òkiti àlapa. 26 Nitorina ni awọn olugbe wọn fi ṣe alainipa, a daiyàfo wọn nwọn si dãmu; nwọn dàbi koriko igbẹ́, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko li ori ile, ati bi ọkà ti o rẹ̀ danù ki o to dàgba soke. 27 Ṣugbọn emi mọ̀ ijoko rẹ, ati ijadelọ rẹ, ati bibọ̀ rẹ, ati ikannu rẹ si mi. 28 Nitori ikánnu rẹ si mi ati irera rẹ de eti mi, nitorina li emi o fi ìwọ̀ mi kọ́ ọ ni imu, ati ijanu mi si ẹnu rẹ, emi o si yi ọ pada si ọ̀na na ti iwọ ti ba wá. 29 Eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun ni, ati li ọdun keji eyiti o hù ninu ọkanna; ati li ọdun kẹta ẹ fun irúgbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba ajara, ki ẹ si jẹ eso rẹ̀. 30 Iyokù ile Juda ti o salà yio si tún ta gbòngbo si isàlẹ, yio si so eso li òke. 31 Nitori lati Jerusalemu li awọn iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o salà lati oke Sioni jade: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni yio ṣe eyi. 32 Nitori bayi li Oluwa wi niti ọba Assiria, On kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio mu asà wá iwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio mọ odi tì i yika. 33 Ọna na ti o ba wá, ọkanna ni yio ba pada lọ, kì yio si wá si ilu yi, li Oluwa wi. 34 Nitori emi o da abò bò ilu yi, lati gbà a, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi. 35 O si ṣe li oru na ni angeli Oluwa jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan le ẹgbẹ̃dọgbọn enia ni ibùbo awọn ara Assiria: nigbati nwọn si dide ni kutukutu owurọ, kiyesi i, okú ni gbogbo wọn jasi. 36 Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si pada, o si joko ni Ninefe. 37 O si ṣe, bi o ti mbọ̀riṣa ni ile Nisroku oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣareseri awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a: nwọn si sa lọ si ilẹ Armenia. Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 20

Àìsàn Hesekaya Ọba, ati Ìwòsàn Rẹ̀

1 LI ọjọ wọnni ni Hesekiah ṣe aisàn de oju-ikú. Isaiah woli ọmọ Amosi si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́; nitoriti iwọ o kú, iwọ kì yio si yè. 2 Nigbana ni o yi oju rẹ̀ pada si ogiri, o si gbadura si Oluwa, wipe, 3 Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, ranti nisisiyi bi emi ti rìn niwaju rẹ ninu otitọ ati ninu aiya pipe, ti mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún gidigidi. 4 O si ṣe, ki Isaiah ki o to jade si ãrin agbalá-ãfin, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe, 5 Tun pada, ki o si wi fun Hesekiah olori awọn enia mi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ: kiyesi i, emi o wò ọ sàn: ni ijọ kẹta iwọ o gòke lọ si ile Oluwa. 6 Emi o si bù ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ: emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria, emi o si dãbò bò ilu yi, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi. 7 Isaiah si wipe, Mu odidi ọ̀pọtọ. Nwọn si mu u, nwọn si fi le õwo na, ara rẹ̀ si da. 8 Hesekiah si wi fun Isaiah pe, Kini yio ṣe àmi pe Oluwa yio wò mi sàn, ati pe emi o gòke lọ si ile Oluwa ni ijọ kẹta? 9 Isaiah si wipe, Àmi yi ni iwọ o ni lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti on ti sọ: ki ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa ni, tabi ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa? 10 Hesekiah si dahùn wipe, Ohun ti o rọrùn ni fun ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa: bẹ̃kọ, ṣugbọn jẹ ki ojiji ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa. 11 Isaiah woli si kepè Oluwa; on si mu ojiji pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa, nipa eyiti o ti sọ̀kalẹ ninu agogo-õrùn Ahasi.

Àwọn Iranṣẹ láti Babilonii

12 Li akokò na ni Berodaki-Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babeli, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitoriti o ti gbọ́ pe Hesekiah ti ṣe aisàn. 13 Hesekiah si fi eti si ti wọn, o si fi gbogbo ile iṣura ohun iyebiye rẹ̀ hàn wọn, fadakà, ati wura, ati turari, ati ororo iyebiye, ati gbogbo ile ohun ihamọra rẹ̀, ati gbogbo eyiti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si nkan ni ile rẹ̀, tabi ni gbogbo ijọba rẹ̀, ti Hesekiah kò fi hàn wọn. 14 Nigbana ni Isaiah woli wá si ọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kili awọn ọkunrin wọnyi wi? ati nibo ni nwọn ti wá si ọdọ rẹ? Hesekiah si wipe, Ilu òkere ni nwọn ti wá, ani lati Babeli: 15 On si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn wipe, Gbogbo nkan ti mbẹ ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkan ninu iṣura mi ti emi kò fi hàn wọn. 16 Isaiah si wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa. 17 Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, ti a o kó gbogbo nkan ti mbẹ ninu ile rẹ, ati eyiti awọn baba rẹ ti tò jọ titi di oni, lọ si Babeli: ohun kan kì yio kù, li Oluwa wi. 18 Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade wá, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ; nwọn o si mã ṣe iwẹ̀fa li ãfin ọba Babeli. 19 Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere li ọ̀rọ Oluwa ti iwọ sọ. On si wipe, kò ha dara bi alafia ati otitọ ba wà lọjọ mi?

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Hesekaya

20 Ati iyokù iṣe Hesekiah ati gbogbo agbara rẹ̀, ati bi o ti ṣe adagun omi, ati ọ̀na omi na, ti o si mu omi wá sinu ilu, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 21 Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Manasse ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 21

Manase, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mejila ni Manasse nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hefsiba. 2 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi iṣe-irira ti awọn keferi, ti Oluwa tì jade niwaju awọn ọmọ Israeli. 3 Nitoriti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀ ti parun; o si tẹ́ pẹpẹ fun Baali o si ṣe ere-oriṣa, bi Ahabu, ọba Israeli ti ṣe, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn. 4 O si tẹ́ pẹpẹ ni ile Oluwa, eyiti Oluwa ti sọ pe, Ni Jerusalemu li emi o fi orukọ mi si. 5 On si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li agbalá mejeji ile Oluwa. 6 On si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná, a si mã ṣe akiyesi afọṣẹ, a si mã ṣe alupàyida, a si mã bá awọn okú ati awọn oṣó lò: o hùwa buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu. 7 O si gbé ere oriṣa fifin kalẹ ti o ti ṣe ni ile na ti Oluwa sọ fun Dafidi ati Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, Ni ile yi, ati ni Jerusalemu, ti mo ti yàn ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai: 8 Bẹ̃ni emi kì yio si jẹ ki ẹsẹ̀ Israeli ki o yẹ̀ kuro mọ ni ilẹ ti mo fi fun awọn baba wọn; kiki bi nwọn o ba ṣe akiyesi lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo pa li aṣẹ fun wọn, ati gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi pa li aṣẹ fun wọn. 9 Ṣugbọn nwọn kò feti silẹ: Manasse si tàn wọn lati ṣe buburu jù eyiti awọn orilẹ-ède ti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli ti ṣe. 10 Oluwa si wi nipa awọn woli iranṣẹ rẹ̀ pe, 11 Nitoriti Manasse ọba Juda ti ṣe ohun-irira wọnyi, ti o si ti ṣe buburu jù gbogbo eyiti awọn ọmọ Amori ti ṣe, ti o ti wà ṣãju rẹ̀, ti o si mu ki Juda pẹlu ki o fi awọn ere rẹ̀ dẹṣẹ: 12 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Kiyesi i, emi nmu iru ibi bayi wá sori Jerusalemu ati Juda, ti ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ, eti rẹ̀ mejeji yio ho. 13 Emi o si nà okùn Samaria lori Jerusalemu, ati òjé-idiwọ̀n ile Ahabu: emi o si nù Jerusalemu bi enia ti nnù awokoto, o nnù u, o si ndori rẹ̀ kodò. 14 Emi o si kọ̀ iyokù awọn ini mi silẹ, emi o si fi wọn le awọn ọ̀ta wọn lọwọ; nwọn o si di ikogun ati ijẹ fun gbogbo awọn ọ̀ta wọn. 15 Nitori nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju mi, ti nwọn si ti mu mi binu, lati ọjọ ti awọn baba wọn ti jade kuro ni Egipti, ani titi di oni yi. 16 Pẹlupẹlu Manasse ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ pupọjù, titi o fi kún Jerusalemu lati ikangun ikini de ekeji; lẹhin ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o mu Juda ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju Oluwa. 17 Ati iyokù iṣe Manasse, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ṣẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 18 Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ninu ọgba-ile rẹ̀, ninu ọgba Ussa: Amoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Amoni Ọba Juda

19 Ẹni ọdun mejilelogun ni Amoni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun meji ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Mesullemeti, ọmọbinrin Harusi ti Jotba. 20 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi baba rẹ̀ Manasse ti ṣe. 21 O si rìn li ọ̀na gbogbo ti baba rẹ̀ rìn, o si sìn awọn ere ti baba rẹ̀ sìn, o si bọ wọn: 22 On si kọ̀ OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ, kò si rìn li ọ̀na Oluwa. 23 Awọn iranṣẹ Amoni si dìtẹ si i, nwọn si pa ọba ni ile rẹ̀. 24 Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o dìtẹ si Amoni ọba: awọn enia ilẹ na si fi Josiah ọmọ rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀. 25 Ati iyokù iṣe Amoni ti o ti ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 26 A si sìn i ni isà okú rẹ̀ ninu ọgba Ussa: Josiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Ọba 22

Josaya, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mẹjọ ni Josiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkanlelọgbọ̀n ni Jerusalemu, Orukọ iya rẹ̀ ni Jedida, ọmọbinrin Adaiah ti Boskati. 2 On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa o si rìn li ọ̀na Dafidi baba rẹ̀ gbogbo, kò si yipada si apa ọ̀tún tabi si apa òsi.

Wọ́n rí Ìwé Òfin

3 O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe, 4 Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia: 5 Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe. 6 Fun awọn gbẹnagbẹna, ati fun awọn akọle, ati awọn ọ̀mọle, lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tún ile na ṣe. 7 Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ. 8 Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a. 9 Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa. 10 Ṣafani akọwe si fi hàn ọba, pe, Hilkiah alufa fi iwe kan le mi lọwọ. Ṣafani si kà a niwaju ọba. 11 O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ inu iwe ofin na, o si fà aṣọ rẹ̀ ya. 12 Ọba si paṣẹ fun Hilkiah alufa, ati Ahikamu ọmọ Ṣafani, ati Akbori ọmọ Mikaiah, ati Ṣafani akọwe, ati Asahiah iranṣẹ ọba wipe, 13 Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn enia, ati fun gbogbo Juda, niti ọ̀rọ iwe yi ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti o rú si wa, nitori awọn baba wa kò fi eti si ọ̀rọ iwe yi, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọwe silẹ fun wa. 14 Bẹ̃ni Hilkiah alufa, ati Ahikamu, ati Akbori, ati Ṣafani, ati Asahiah tọ̀ Hulda woli obinrin lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikfa, ọmọ Harhasi, alabojuto aṣọ (njẹ on ngbe Jerusalemu niha keji); nwọn si ba a sọ̀rọ. 15 On si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Sọ fun ọkunrin ti o rán nyin si mi pe, 16 Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi bá ibiyi, ati bá awọn ara ilu na, ani gbogbo ọ̀rọ iwe na ti ọba Juda ti kà. 17 Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti nsun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina ibinu mi yio rú si ibi yi, kì yio si rọlẹ. 18 Ṣugbọn fun ọba Juda ti o rán nyin wá ibère lọdọ Oluwa, bayi li ẹnyin o sọ fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́: 19 Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, nigbati iwọ gbọ́ eyiti mo sọ si ibi yi, ati si awọn ara ilu na pe, nwọn o di ahoro ati ẹni-ègun, ti iwọ si fà aṣọ rẹ ya, ti o si sọkun niwaju mi; emi pẹlu ti gbọ́ tirẹ, li Oluwa wi. 20 Nitorina kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ sinu isà-okú rẹ li alafia; oju rẹ kì o si ri gbogbo ibi ti emi o mu wá bá ibi yi. Nwọn si tún mu èsi fun ọba wá.

2 Ọba 23

Josaya pa Ìbọ̀rìṣà Run

1 ỌBA si ranṣẹ, nwọn si pè gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ sọdọ rẹ̀. 2 Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo awọn enia Juda ati gbogbo olugbe Jerusalemu pẹlu rẹ̀, ati awọn alufa, ati awọn woli ati gbogbo enia, ati ewe ati àgba: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn. 3 Ọba si duro ni ibuduro na, o si dá majẹmu niwaju Oluwa, lati mã fi gbogbo aìya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati mu ọ̀rọ majẹmu yi ṣẹ, ti a ti kọ ninu iwe yi. Gbogbo awọn enia si duro si majẹmu na. 4 Ọba si paṣẹ fun Hilkiah olori alufa, ati awọn alufa ẹgbẹ keji, ati awọn alabojuto iloro, lati kó gbogbo ohun-èlo ti a ṣe fun Baali, ati fun ere òriṣa, ati fun gbogbo ogun ọrun jade kuro ni tempili Oluwa: o si sun wọn lẹhin ode Jerusalemu ninu pápa Kidroni, o si kó ẽru wọn lọ si Beteli. 5 O si dá awọn baba-loriṣa lẹkun, ti awọn ọba Juda ti yàn lati ma sun turari ni ibi giga ni ilu Juda wọnni, ati ni ibi ti o yi Jerusalemu ka; awọn pẹlu ti nsun turari fun Baali, fun õrùn, ati fun òṣupa, ati fun awọn àmi mejila ìrawọ, ati fun gbogbo ogun ọrun. 6 O si gbé ere-oriṣa jade kuro ni ile Oluwa, sẹhin ode Jerusalemu lọ si odò Kidroni, o si sun u nibi odò Kidroni, o si lọ̀ ọ lũlu, o si dà ẽrú rẹ̀ sori isà-okú awọn ọmọ enia na. 7 O si wó ile awọn ti nhù ìwa panṣaga, ti mbẹ leti ile Oluwa, nibiti awọn obinrin wun aṣọ-agọ fun ere-oriṣa. 8 O si kó gbogbo awọn alufa jade kuro ni ilu Juda wọnni, o si sọ ibi giga wọnni di ẽri nibiti awọn alufa ti sun turari, lati Geba titi de Beer-ṣeba, o si wó ibi giga ẹnu-ibodè wọnni ti mbẹ ni atiwọ̀ ẹnu-ibodè Joṣua bãlẹ ilu, ti mbẹ lapa osi ẹni, ni atiwọ̀ ẹnu-ibode ilu. 9 Ṣugbọn awọn alufa ibi giga wọnni kò gòke wá si ibi pẹpẹ Oluwa ni Jerusalemu, ṣugbọn nwọn jẹ ninu àkara alaiwu lãrin awọn arakunrin wọn. 10 On si sọ Tofeti di ẽri, ti mbẹ ni afonifojì awọn ọmọ Hinnomu, ki ẹnikan ki o máṣe mu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là ãrin iná kọja fun Moleki. 11 O si mu ẹṣin wọnni kuro ti awọn ọba Juda ti fi fun õrun, ni atiwọ̀ inu ile Oluwa lẹba iyẹ̀wu Natan-meleki iwẹ̀fa, ti o ti wà ni agbegbe tempili, o si fi iná sun kẹkẹ́ õrun wọnni. 12 Ati pẹpẹ wọnni ti mbẹ lori iyara òke Ahasi, ti awọn ọba Juda ti tẹ́, ati pẹpẹ wọnni ti Manasse ti tẹ́ li ãfin mejeji ile Oluwa ni ọba wó lulẹ, o si yara lati ibẹ, o si da ekuru wọn sinu odò Kidroni. 13 Ati ibi giga wọnni ti o wà niwaju Jerusalemu, ti o wà li ọwọ ọtún òke idibàjẹ, ti Solomoni ọba Israeli ti kọ́ fun Aṣtoreti ohun irira awọn ara Sidoni, ati fun Kemoṣi ohun irira awọn ara Moabu, ati fun Milkomu ohun-irira awọn ọmọ Ammoni li ọba sọ di ẽri. 14 O si fọ́ awọn ere na tũtu, o si wó awọn ere-oriṣa lulẹ, o si fi egungun enia kún ipò wọn. 15 Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na. 16 Bi Josiah si ti yira pada, o ri awọn isà-okú ti o wà lori òke, o si ranṣẹ, o si kó awọn egungun lati inu isà wọnni kuro, o si sun wọn lori pẹpẹ na, o si sọ ọ di ẽri, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti enia Ọlọrun nì ti kede, ẹniti o kede ọ̀ro wọnyi. 17 Nigbana li o wipe, Ọwọ̀n isa-okú wo li eyi ti mo ri nì? Awọn enia ilu na si sọ fun u pe, Isà-okú enia Ọlọrun nì ni, ti o ti Juda wá, ti o si kede nkan wọnyi ti iwọ ti ṣe si pẹpẹ Beteli. 18 On si wipe, Jọwọ rẹ̀; máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mu egungun rẹ̀ kuro. Bẹ̃ni nwọn jọwọ egungun rẹ̀ lọwọ, pẹlu egungun woli ti o ti Samaria wá. 19 Ati pẹlu gbogbo ile ibi-giga wọnni ti o wà ni ilu Samaria wọnni, ti awọn ọba Israeli ti kọ́ lati rú ibinu Oluwa soke ni Josiah mu kuro, o si ṣe si wọn gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti o ṣe ni Beteli. 20 O si pa gbogbo awọn alufa ibi-giga wọnni ti o wà nibẹ lori awọn pẹpẹ na, o si sun egungun enia lori wọn, o si pada si Jerusalemu.

Josaya Ọba ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá

21 Ọba si paṣẹ fun gbogbo enia, wipe, Pa irekọja mọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin, bi a ti kọ ọ ninu iwe majẹmu yi. 22 Nitõtọ a kò ṣe iru irekọja bẹ̃ lati ọjọ awọn onidajọ ti ndajọ ni Israeli, tabi ni gbogbo ọjọ awọn ọba Israeli tabi awọn ọba Juda; 23 Ṣugbọn li ọdun kejidilogun Josiah ọba, ni a pa irekọja yi mọ́ fun Oluwa ni Jerusalemu.

Àwọn Àtúnṣe Mìíràn tí Josaya Ṣe

24 Ati pẹlu awọn ti mba awọn okú lò, ati awọn oṣo, ati awọn ere, ati awọn oriṣa, ati gbogbo irira ti a ri ni ilẹ Juda ati ni Jerusalemu ni Josiah kó kuro, ki o le mu ọ̀rọ ofin na ṣẹ ti a ti kọ sinu iwe ti Hilkiah alufa ri ni ile Oluwa. 25 Kò si si ọba kan ṣãju rẹ̀, ti o dabi rẹ̀, ti o yipada si Oluwa tinutinu ati tọkàntọkàn ati pẹlu gbogbo agbara rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo ofin Mose; bẹ̃ni lẹhin rẹ̀, kò si ẹnikan ti o dide ti o dàbi rẹ̀. 26 Ṣugbọn Oluwa kò yipada kuro ninu mimuná ibinu nla rẹ̀, eyiti ibinu rẹ̀ fi ràn si Juda, nitori gbogbo imunibinu ti Manasse ti fi mu u binu. 27 Oluwa si wipe, Emi o si mu Juda kuro loju mi pẹlu, bi mo ti mu Israeli kuro, emi o si ta ilu Jerusalemu yi nù, ti mo ti yàn, ati ile eyiti mo wipe, Orukọ mi yio wà nibẹ.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya

28 Ati iyokù iṣe Josiah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 29 Li ọjọ rẹ̀ ni Farao-Neko ọba Egipti dide ogun si ọba Assiria li odò Euferate: Josiah ọba si dide si i; on si pa a ni Megiddo, nigbati o ri i. 30 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e li okú ninu kẹkẹ́ lati Megiddo lọ, nwọn si mu u wá si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni isà-okú on tikalarẹ̀. Awọn enia ilẹ na si mu Jehoahasi ọmọ Josiah, nwọn si fi ororo yàn a, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀.

Jehoahasi, Ọba Juda

31 Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna, 32 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe. 33 Farao-Neko si fi i sinu idè ni Ribla, ni ilẹ Hamati, ki o má ba jọba ni Jerusalemu; o si fi ilẹ na si abẹ isìn li ọgọrun talenti fadakà, ati talenti wura. 34 Farao-Neko si fi Eliakimu ọmọ Josiah jẹ ọba ni ipò Josiah baba rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu, o si mu Jehoahasi kuro; on si wá si Egipti, o si kú nibẹ.

Jehoiakimu Ọba Juda

35 Jehoiakimu si fi fadakà ati wura na fun Farao; ṣugbọn o bu owo-odè fun ilẹ na lati san owo na gẹgẹ bi ofin Farao: o fi agbara gbà fadakà ati wurà na lọwọ awọn enia ilẹ na, lọwọ olukuluku gẹgẹ bi owo ti a bù fun u, lati fi fun Farao-Neko. 36 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jehoiakimu nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Sebuda, ọmọbinrin Bedaiah ti Ruma. 37 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.

2 Ọba 24

1 LI ọjọ rẹ̀ ni Nebukadnessari ọba Babeli gòke wá, Jehoiakimu si di iranṣẹ rẹ̀ li ọdun mẹta: nigbana li o pada o si ṣọ̀tẹ si i. 2 Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli. 3 Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe; 4 Ati nitori ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ ti o ta silẹ pẹlu: nitoriti o fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kún Jerusalemu; ti Oluwa kò fẹ darijì. 5 Ati iyokù iṣe Jehoiakimu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? 6 Bẹ̃ni Jehoiakimu sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Jehoiakini ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. 7 Ọba Egipti kò si tun jade kuro ni ilẹ rẹ̀ mọ; nitori ọba Babeli ti gbà gbogbo eyiti iṣe ti ọba Egipti lati odò Egipti wá titi de odò Euferate.

Jehoiakini, Ọba Juda

8 Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Nehuṣta, ọmọbinrin Elnatani ti Jerusalemu. 9 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe. 10 Li akokò na, awọn iranṣẹ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá si Jerusalemu, a si dotì ilu na. 11 Nebukadnessari ọba Babeli si de si ilu na, nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si dotì i. 12 Jehoiakini ọba Juda si jade tọ̀ ọba Babeli lọ, on, ati iya rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn iwẹfa rẹ̀: ọba Babeli si mu u li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀. 13 O si kó gbogbo iṣura ile Oluwa lọ kuro nibẹ, ati iṣura ile ọba, o si ké gbogbo ohun-èlo wura wẹwẹ ti Solomoni ọba Israeli ti ṣe ni tempili Oluwa, bi Oluwa ti sọ. 14 O si kó gbogbo Jerusalemu lọ, ati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo awọn alagbara akọni enia, ani ẹgbãrun igbèkun, ati gbogbo awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹ̀dẹ: kò kù ẹnikan, bikòṣe iru awọn ti o jẹ talakà ninu awọn enia ilẹ na. 15 O si mu Jehoiakini lọ si Babeli, ati iya ọba, ati awọn obinrin ọba, ati awọn iwẹ̀fa rẹ̀, ati awọn alagbara ilẹ na, awọn wọnyi li o kó ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli. 16 Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọla, ẹ̃dẹgbãrin, ati awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹdẹ ẹgbẹrun, gbogbo awọn ti o li agbara ti o si yẹ fun ogun, ani awọn li ọba Babeli kó ni igbèkun lọ si Babeli. 17 Ọba Babeli si fi Mattaniah arakunrin baba rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Sedekiah.

Sedekaya, Ọba Juda

18 Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna. 19 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe. 20 Nitori nipa ibinu Oluwa li o ṣẹ si Jerusalemu ati Juda, titi o fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀; Sedekiah si ṣọ̀tẹ si ọba Babeli.

2 Ọba 25

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣù kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣù, ni Nebukadnessari ọba Babeli de, on, ati gbogbo ogun rẹ̀, si Jerusalemu, o si dotì i; nwọn si mọdi tì i yika kiri. 2 A si dotì ilu na titi di ọdun ikọkanla Sedekiah. 3 Ati li ọjọ kẹsan oṣù kẹrin, iyàn mu gidigidi ni ilu, kò si si onjẹ fun awọn enia ilẹ na. 4 Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ. 5 Ogun awọn ara Kaldea si lepa ọba, nwọn si ba a ni pẹ̀tẹlẹ Jeriko: gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀. 6 Bẹ̃ni nwọn mu ọba, nwọn si mu u gòke lọ si ọdọ ọba Babeli ni Ribla; nwọn si sọ ọ̀rọ idajọ lori rẹ̀. 7 Nwọn si pa awọn ọmọ Sedekiah li oju rẹ̀, nwọn si fọ Sedekiah li oju, nwọn si fi ẹwọn idẹ dè e, nwọn si mu u lọ si Babeli.

Pípa Tẹmpili Run

8 Ati li oṣù karun, li ọjọ keje oṣù, ti iṣe ọdun ikọkandilogun Nebukadnessari ọba, ọba Babeli, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ, iranṣẹ ọba Babeli, wá si Jerusalemu: 9 O si fi ile Oluwa joná, ati ile ọba, ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile enia nla li o fi iná sun. 10 Gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti o wà lọdọ olori ẹ̀ṣọ, si wó odi Jerusalemu palẹ yika kiri. 11 Ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ati awọn isansa ti o ya tọ̀ ọba, Babeli lọ, pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ti o kù, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ kó lọ. 12 Ṣugbọn olori ẹ̀ṣọ fi awọn talakà ilẹ na silẹ, lati mã ṣe alabojuto àjara ati lati mã ṣe aroko. 13 Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ ni ile Oluwa, ati ijoko wọnni, ati agbada-nla idẹ ti o wà ni ile Oluwa, li awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó idẹ wọn lọ si Babeli. 14 Ati ikòko wọnni, ati ọkọ wọnni, ati alumagàji fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun-èlo wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ, ni nwọn kó lọ. 15 Ati ohun ifọnná wọnni, ati ọpọ́n wọnni, eyi ti iṣe ti wura, ni wura, ati eyi ti iṣe ti fadakà ni fadakà, ni olori ẹ̀ṣọ kó lọ. 16 Awọn ọ̀wọn meji, agbada-nla kan, ati ijoko wọnni ti Solomoni ti ṣe fun ile Oluwa; idẹ ni gbogbo ohun-èlo wọnyi, alaini ìwọn ni. 17 Giga ọwọ̀n kan ni igbọ̀nwọ mejidilogun, ati ọnà-ori rẹ̀ idẹ ni: ati giga ọnà-ori na ni igbọ̀nwọ mẹta; ati iṣẹ wiwun na, ati awọn pomegranate ti o wà lori ọnà-ori na yika kiri, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹgẹ bi awọn wọnyi si ni ọwọ̀n keji pẹlu iṣẹ wiwun.

A kó àwọn eniyan Juda lọ sí Babilonii

18 Olori ẹ̀ṣọ si mu Seraiah olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah alufa keji, ati awọn olùṣọ iloro mẹta. 19 Ati lati inu ilu, o mu iwẹ̀fa kan ti a fi ṣe olori awọn ologun, ati ọkunrin marun ninu awọn ti o wà niwaju ọba, ti a ri ni ilu, ati akọwe olori ogun, ti ntò awọn enia ilẹ na, ati ọgọta ọkunrin ninu awọn enia ilẹ na ti a ri ni ilu. 20 Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ si kó awọn wọnyi, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla. 21 Ọba Babeli si kọlù wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.

Gedalaya, Gomina Juda

22 Ati awọn enia ti o kù ni ilẹ Juda, ti Nebukadnessari ọba Babeli fi silẹ, ani, o fi Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, jẹ bãlẹ wọn. 23 Nigbati gbogbo awọn olori ogun, awọn ati awọn ọkunrin wọn, si gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah jẹ bãlẹ, nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ati Johanani ọmọ Karea, ati Seraiah ọmọ Tanhumeti ara Netofati, ati Jaasaniah ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn. 24 Gedaliah si bura fun wọn, ati fun awọn ọkunrin wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru lati sìn awọn ara Kaldea: ẹ mã gbe ilẹ na, ki ẹ si mã sìn ọba Babeli; yio si dara fun nyin. 25 O si ṣe li oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama ninu iru ọmọ ọba, wá ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, o si kọlù Gedaliah, o si kú, ati awọn ara Juda ati awọn ara Kaldea ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Mispa. 26 Ati gbogbo enia, ti ewe ti àgba, ati awọn olori ogun, si dide, nwọn si wá si Egipti: nitoriti nwọn bẹ̀ru ara Kaldea.

A dá Jehoiakini Sílẹ̀ kúrò Ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

27 O si ṣe li ọdun kẹtadilogoji igbèkun Jehoiakini ọba Juda, li oṣù kejila, li ọjọ kẹtadilọgbọn oṣù, Efil-merodaki ọba Babeli, li ọdun ti o bẹ̀rẹ si ijọba, o gbé ori Jehoiakini ọba Juda soke kuro ninu tubu; 28 O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbé ìtẹ rẹ̀ ga jù ìtẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli. 29 O si pàrọ awọn aṣọ tubu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀. 30 Ati ipin onjẹ tirẹ̀, jẹ ipin onjẹ ti ọba nfi fun u nigbagbogbo, iye kan li ojojumọ, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

1 Kronika 1

Ìran Adamu títí Dé Orí Abrahamu

1 ADAMU, Seti, Enoṣi, 2 Kenani, Mahalaleeli, Jeredi, 3 Henoki, Metusela, Lameki, 4 Noa, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti, 5 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi, 6 Ati awọn ọmọ Gomeri; Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma. 7 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu. 8 Awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, Puti, ati Kenaani. 9 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Ṣeba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka. Ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba ati Dedani. 10 Kuṣi si bi Nimrodu: on bẹ̀rẹ si di alagbara li aiye. 11 Misraimu si bi Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu, 12 Ati Patrusimu, ati Kasluhimu, (lọdọ ẹniti awọn ara Filistia ti wá,) ati Kaftorimu. 13 Kenaani si bi Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti, 14 Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi, 15 Ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini, 16 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati. 17 Awọn ọmọ Ṣemu; Elamu, ati Assuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu, ati Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Meṣeki. 18 Arfaksadi si bi Ṣela; Ṣela si bi Eberi. 19 Ati fun Eberi li a bi ọmọkunrin meji: orukọ ọkan ni Pelegi; nitori li ọjọ rẹ̀ li a pin aiye niya: orukọ arakunrin rẹ̀ si ni Joktani. 20 Joktani si bi Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera, 21 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla, 22 Ati Ebali, ati Abimaeli, ati Ṣeba, 23 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Joktani. 24 Ṣemu, Arfaksadi, Ṣela, 25 Eberi, Pelegi, Reu, 26 Serugu, Nahori, Tera, 27 Abramu; on na ni Abrahamu,

Ìran Iṣimaeli

28 Awọn ọmọ Abrahamu; Isaaki, ati Iṣmaeli. 29 Wọnyi ni iran wọn: akọbi Iṣmaeli, Nebaioti; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu, 30 Miṣma, ati Duma, Massa, Hadadi, ati Tema, 31 Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema. Wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli. 32 Ati awọn ọmọ Ketura, obinrin Abrahamu: on bi Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaki, ati Ṣua. Ati awọn ọmọ Jokṣani: Ṣeba, ati Dedani. 33 Ati awọn ọmọ Midiani: Efa, ati Eferi, ati Henoki, ati Abida, ani Eldaa. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Ketura.

Àwọn Ìran Esau

34 Abrahamu si bi Isaaki. Awọn ọmọ Isaaki; Esau ati Israeli. 35 Awọn ọmọ Esau; Elifasi, Reueli, ati Jeusi, ati Jaalamu, ati Kora. 36 Awọn ọmọ Elifasi; Temani, ati Omari, Sefi, ati Gatamu, Kenasi, ati Timna, ati Amaleki. 37 Awọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma, ati Missa.

Àwọn tí ń gbé Edomu tẹ́lẹ̀

38 Ati awọn ọmọ Seiri; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, ati Diṣoni, ati Esari, ati Diṣani. 39 Ati awọn ọmọ Lotani; Hori, ati Homamu: Timna si ni arabinrin Lotani. 40 Awọn ọmọ Ṣobali; Aliani, ati Manahati, ati Ebali, Ṣefi, ati Onamu. Ati awọn ọmọ Sibeoni; Aiah, ati Ana. 41 Awọn ọmọ Ana; Diṣoni. Ati awọn ọmọ Diṣoni; Amrani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani. 42 Awọn ọmọ Eseri; Bilhani, ati Safani, ati Jakani. Awọn ọmọ Diṣani; Usi, ati Arani.

Àwọn Ọba Edomu

43 Wọnyi si ni awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan to jẹ lori awọn ọmọ Israeli: Bela ọmọ Beori: orukọ ilu rẹ̀ si ni Dinhaba. 44 Nigbati Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀. 45 Nigbati Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ awọn ara Temani si jọba ni ipò rẹ̀. 46 Nigbati Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ti o kọlu Midiani ni ìgbẹ Moabu, jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Afiti. 47 Nigbati Hadadi kú, Samla ti Masreka jọba ni ipò rẹ̀. 48 Nigbati Samla kú, Ṣaulu ti Rehoboti leti odò jọba ni ipò rẹ̀. 49 Nigbati Ṣaulu kú, Baal-hanani, ọmọ Akbori, jọba ni ipò rẹ̀. 50 Nigbati Baal-hanani kú, Hadadi si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Pai; orukọ aya rẹ̀ si ni Mehetabeeli, ọmọbinrin Matredi, ọmọbinrin Mesahabu. 51 Hadadi si kú. Awọn bãlẹ Edomu ni; Timna bãlẹ, Aliah bãlẹ, Jeteti bãlẹ. 52 Aholibama bãlẹ, Ela bãlẹ, Pinoni bãlẹ, 53 Kenasi bãlẹ, Temani bãlẹ, Mibsari bãlẹ, 54 Magdieli bãlẹ, Iramu bãlẹ. Wọnyi ni awọn bãlẹ Edomu.

1 Kronika 2

Àwọn Arọmọdọmọ Juda

1 WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni, 2 Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri. 3 Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a. 4 Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun. 5 Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli. 6 Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun. 7 Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀. 8 Awọn ọmọ Etani; Asariah.

Ìran Dafidi Ọba

9 Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai. 10 Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda; 11 Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi. 12 Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse, 13 Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta. 14 Netanneeli ẹkẹrin, Raddai ẹkarun, 15 Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje: 16 Awọn arabinrin wọn ni Seruiah ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruiah; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaeli, mẹta. 17 Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.

Ìran Hesironi

18 Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni. 19 Nigbati Asuba kú, Kalebu mu Efrati, ẹniti o bi Huri fun u. 20 Huri si bi Uru, Uru si bi Besaleeli. 21 Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u. 22 Segubu si bi Jairi, ti o ni ilu mẹtalelogun ni ilẹ Gileadi. 23 Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi. 24 Ati lẹhin igbati Hesroni kú ni ilu Kaleb-Efrata, ni Abiah aya Hesroni bi Aṣuri baba Tekoa fun u.

Àwọn Ìran Jerameeli

25 Ati awọn ọmọ Jerahmeeli, akọbi Hesroni, ni Rama akọbi, ati Buna, ati Oreni, ati Osemu, ati Ahijah. 26 Jerahmeeli si ni obinrin miran pẹlu, orukọ ẹniti ijẹ Atara; on ni iṣe iya Onamu. 27 Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri. 28 Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri. 29 Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u. 30 Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ. 31 Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai. 32 Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ. 33 Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli. 34 Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha. 35 Ṣeṣani si fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Jarha iranṣẹ rẹ̀ li aya; on si bi Attai fun u. 36 Attai si bi Natani, Natani si bi Sabadi, 37 Sabadi si bi Eflali, Eflali si bi Obedi, 38 Obedi si bi Jehu, Jehu si bi Asariah, 39 Asariah si bi Helesi, Helesi si bi Elasa, 40 Elasa si bi Sisamai, Sisamai si bi Ṣallumu, 41 Ṣallumu si bi Jekamiah, Jekamiah si bi Eliṣama.

Àwọn Ìran Kalebu Yòókù

42 Awọn ọmọ Kalebu arakunrin Jerahmeeli si ni Meṣa akọbi rẹ̀, ti iṣe baba Sifi; ati awọn ọmọ Mareṣa baba Hebroni. 43 Awọn ọmọ Hebroni; Kora, ati Tappua, ati Rekemu, ati Ṣema. 44 Ṣema si bi Rahamu, baba Jorkeamu: Rekemu si bi Ṣammai. 45 Ati ọmọ Ṣammai ni Maoni: Maoni si ni baba Bet-suri. 46 Efa obinrin Kalebu si bi Harani, ati Mosa, ati Gasesi: Harani si bi Gasesi. 47 Ati awọn ọmọ Jahdai; Regemu, ati Jotamu, ati Geṣamu, ati Peleti, ati Efa, ati Ṣaafu. 48 Maaka obinrin Kalebu bi Ṣeberi, ati Tirhana. 49 On si bi Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena, ati baba Gibea: ọmọbinrin Kalebu si ni Aksa. 50 Wọnyi li awọn ọmọ Kalebu ọmọ Huri, akọbi Efrata; Ṣobali baba Kirjat-jearimu, 51 Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi. 52 Ati Ṣobali baba Kirjat-jearimu ni ọmọ; Haroe, ati idaji awọn ara Manaheti. 53 Ati awọn idile Kirjat-jearimu; awọn ara Itri, ati awọn ara Puti, ati awọn ara Ṣummati, ati awọn ara Misrai; lọdọ wọn li awọn ara Sareati, ati awọn ara Ẹstauli ti wá. 54 Awọn ọmọ Salma; Betlehemu, ati awọn ara Netofati, Ataroti, ile Joabu, ati idaji awọn ara Manahati, awọn ara Sori. 55 Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.

1 Kronika 3

Àwọn Ọmọ Dafidi Ọba

1 WỌNYI li awọn ọmọ Dafidi, ti a bi fun u ni Hebroni; akọbi Amnoni, lati ọdọ Ahinoamu ara Jesreeli; ekeji Danieli, lati ọdọ Abigaili ara Karmeli; 2 Ẹkẹta, Absalomu ọmọ Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Gesuri; ẹkẹrin, Adonijah ọmọ Haggiti. 3 Ẹkarun, Ṣefatiah lati ọdọ Abitali; ẹkẹfa Itreamu lati ọdọ Ẹgla aya rẹ̀. 4 Awọn mẹfa wọnyi li a bi fun u ni Hebroni; nibẹ li o si jọba li ọdun meje on oṣù mẹfa: ati ni Jerusalemu li o jọba li ọdun mẹtalelọgbọn. 5 Wọnyi li a si bi fun u ni Jerusalemu; Ṣimea, ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, mẹrin, lati ọdọ Batṣua ọmọbinrin Ammieli: 6 Abhari pẹlu, ati Eliṣama, ati Elifeleti, 7 Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia, 8 Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifeleti mẹsan. 9 Wọnyi ni gbogbo awọn ọmọ Dafidi, laika awọn ọmọ àle rẹ̀, ati Tamari arabinrin wọn.

Ìran Solomoni Ọba

10 Ọmọ Solomoni si ni Rehoboamu, Abia ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀. 11 Joramu ọmọ rẹ̀, Ahasiah ọmọ rẹ̀, Joaṣi ọmọ rẹ̀, 12 Amasiah ọmọ rẹ̀, Asariah ọmọ rẹ̀, Jotamu ọmọ rẹ̀, 13 Ahasi ọmọ rẹ̀, Hesekiah ọmọ rẹ̀, Manasse ọmọ rẹ̀, 14 Amoni ọmọ rẹ̀, Josiah ọmọ rẹ̀. 15 Ati awọn ọmọ Josiah; akọbi Johanani, ekeji Jehoiakimu, ẹkẹta Sedekiah, ẹkẹrin Ṣallumu. 16 Ati awọn ọmọ Jehoiakimu: Jekoniah ọmọ rẹ̀, Sedekiah ọmọ rẹ̀,

Àwọn Ìran Jehoiakini

17 Ati awọn ọmọ Jekoniah; Assiri, Salatieli ọmọ rẹ̀. 18 Malkiramu pẹlu, ati Pedaiah, ati Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama ati Nehabiah, 19 Ati awọn ọmọ Pedaiah; Serubbabeli; ati Ṣimei; ati awọn ọmọ Serubbabeli; Meṣullamu, ati Hananiah, ati Ṣelomiti arabinrin wọn: 20 Ati Haṣuba, ati Oheli, ati Berekiah, ati Hasadiah, Juṣab-hesedi, marun. 21 Ati awọn ọmọ Hananiah; Pelatiah, ati Jesaiah: awọn ọmọ Refaiah, awọn ọmọ Arnani, awọn ọmọ Obadiah, awọn ọmọ Ṣekaniah. 22 Ati awọn ọmọ Ṣekaniah; Ṣemaiah; ati awọn ọmọ Ṣemaiah; Hettuṣi, ati Igeali, ati Bariah, ati Neariah, ati Ṣafati, mẹfa. 23 Ati awọn ọmọ Neariah; Elioenai, ati Hesekiah, ati Asrikamu, meta. 24 Ati awọn ọmọ Elioenai ni, Hodaiah, ati Eliaṣibu, ati Pelaiah, ti Akkubu, ati Johanani, ati Dalaiah, ati Anani, meje.

1 Kronika 4

Ìran Juda

1 AWỌN ọmọ Juda; Faresi, Hesroni, ati Karmi, ati Huri, ati Ṣobali. 2 Reaiah ọmọ Ṣobali si bi Jahati; Jahati si bi Ahumai, ati Lahadi. Wọnyi ni idile awọn ara Sora. 3 Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi: 4 Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu. 5 Aṣuri baba Tekoa si li aya meji, Hela ati Naara. 6 Naara si bi Ahusamu, ati Heferi, ati Temeni, ati Ahaṣtari fun u. Wọnyi li awọn ọmọ Naara. 7 Ati awọn ọmọ Hela ni Sereti, ati Jesoari, ati Etnani. 8 Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu. 9 Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ. 10 Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.

Àwọn ìdílé yòókù

11 Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni. 12 Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka, 13 Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati. 14 Meonotai si bi Ofra: Seraiah si bi Joabu, baba Geharasimu; nitori oniṣọnà ni nwọn. 15 Ati awọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne; Iru, Ela, ati Naamu: ati awọn ọmọ Ela, ani Kenasi. 16 Ati awọn ọmọ Jehaleleeli; Sifu, ati Sifa, Tiria, ati Asareeli. 17 Ati awọn ọmọ Esra ni Jeteri, ati Meredi, ati Eferi, ati Jaloni: on si bi Miriamu, ati Ṣammai, ati Iṣba baba Eṣtemoa. 18 Aya rẹ̀ Jehudijah si bi Jeredi baba Gedori, ati Heberi baba Soke, ati Jekutieli baba Sanoa. Wọnyi si li awọn ọmọ Bitiah ọmọbinrin Farao ti Meredi mu li aya. 19 Ati awọn ọmọ aya Hodiah, arabinrin Nahamu, baba Keila, ara Garmi, ati Eṣtemoa ara Maaka: 20 Awọn ọmọ Ṣimoni si ni Amnoni, ati Rinna, Benhanani, ati Tiloni. Ati awọn ọmọ Iṣi ni, Soheti, ati Bensoheti,

Àwọn Ìran Ṣela

21 Awọn ọmọ Ṣela, ọmọ Juda ni, Eri baba Leka, ati Laada baba Mareṣa ati idile ile awọn ti nwọn nwun aṣọ ọ̀gbọ daradara, ti ile Aṣbea, 22 Ati Jokimu, ati awọn ọkunrin Koseba, ati Joaṣi, ati Sarafu, ti o ni ijọba ni Moabu, ati Jaṣubilehemu. Iwe iranti atijọ ni wọnyi. 23 Wọnyi li awọn amọkoko, ati awọn ti ngbe ãrin ọgba ti odi yika; nibẹ ni nwọn ngbe pẹlu ọba fun iṣẹ rẹ̀.

Àwọn Ìran Simeoni

24 Awọn ọmọ Simeoni ni, Nemueli, ati Jamini, Jaribi, Sera, Ṣauli: 25 Ṣallumu ọmọ rẹ̀, Mibsamu ọmọ rẹ̀, Miṣma ọmọ rẹ̀. 26 Ati awọn ọmọ Miṣma; Hammueli ọmọ rẹ̀, Sakkuri ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀. 27 Ṣimei si ni ọmọkunrin mẹrindilogun, ati ọmọbinrin mẹfa; ṣugbọn awọn arakunrin rẹ̀ kò ni ọmọkunrin pupọ, bẹ̃ni kì iṣe idile wọn gbogbo li o rẹ̀ gẹgẹ bi awọn ọmọ Juda. 28 Nwọn si ngbe Beerṣeba, ati Molada, ati Haṣari-ṣuali, 29 Ati ni Bilha, ati ni Esemu, ati ni Toladi, 30 Ati ni Betueli, ati ni Horma, ati ni Siklagi, 31 Ati ni Bet-markaboti, ati ni Hasar-susimu, ati ni Bet-birei, ati Ṣaaraimu. Awọn wọnyi ni ilu wọn, titi di ijọba Dafidi. 32 Ileto wọn si ni, Etamu, ati Aini, Rimmoni, ati Tokeni, ati Aṣani, ilu marun: 33 Ati gbogbo ileto wọn, ti o wà yi ilu na ka, de Baali. Wọnyi ni ibugbe wọn, ati itan idile wọn. 34 Ati Meṣobabu ati Jamleki, ati Joṣa ọmọ Amasiah. 35 Ati Joeli, ati Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli, 36 Ati Elioenai, ati Jaakoba, ati Jeṣohaiah, ati Asaiah, ati Adieli, ati Jesimieli, ati Benaiah, 37 Ati Sisa ọmọ Ṣifi, ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah; 38 Awọn ti a darukọ wọnyi, ìjoye ni wọn ni idile wọn: ile baba wọn si tan kalẹ gidigidi. 39 Nwọn si wọ̀ oju-ọ̀na Gedori lọ, titi de apa ariwa afonifoji na, lati wá koriko fun agbo ẹran wọn. 40 Nwọn si ri koriko tutù ti o si dara; ilẹ na si gbàye, o si gbe jẹ, o si wà li alafia: nitori awọn ọmọ Hamu li o ti ngbe ibẹ li atijọ. 41 Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn. 42 Omiran ninu wọn, ani ninu awọn ọmọ Simeoni, ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin, lọ si òke Seiri, nwọn ni Pelatiah, ati Neariah, ati Refaiah ati Ussieli, awọn ọmọ Iṣi li olori wọn. 43 Nwọn si kọlù iyokù awọn ara Amaleki, ti nwọn salà, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.

1 Kronika 5

Ìran Reubẹni

1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, (nitori on li akọbi; ṣugbọn, bi o ti ṣepe o ba ẹní baba rẹ̀ jẹ, a fi ogun ibi rẹ̀ fun awọn ọmọ Josefu ọmọ Israeli: a kì yio si ka itan-idile na gẹgẹ bi ipò ibi. 2 Nitori Juda bori awọn arakunrin rẹ̀, ati lọdọ rẹ̀ ni alaṣẹ ti jade wá; ṣugbọn ogún ibi jẹ ti Josefu:) 3 Mo ni, awọn ọmọ Rubeni akọbi Israeli ni Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi. 4 Awọn ọmọ Joeli; Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀, 5 Mika ọmọ rẹ̀, Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀, 6 Beera ọmọ rẹ̀, ti Tiglat-pilneseri ọba Assiria kò ni ìgbekun lọ; ijoye awọn ọmọ Rubeni ni iṣe. 7 Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa idile wọn, nigbati a nkà itàn-idile iran wọn, Jeieli, ati Sekariah ni olori. 8 Ati Bela ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli, ti ngbe Aroeri, ani titi de Nebo ati Baalmeoni: 9 Ati niha ariwa, o tẹ̀do lọ titi de ati-wọ̀ aginju lati odò Eufrate; nitoriti ẹran ọ̀sin wọn pọ̀ si i ni ilẹ Gileadi. 10 Ati li ọjọ Saulu, nwọn ba awọn ọmọ Hagari jagun, ẹniti o ṣubu nipa ọwọ wọn: nwọn si ngbe inu agọ wọn ni gbogbo ilẹ ariwa Gileadi.

Àwọn Ìran Gadi

11 Ati awọn ọmọ Gadi ngbe ọkánkan wọn, ni ilẹ Baṣani titi de Salka: 12 Joeli olori, ati Ṣafamu àtẹle, ati Jaanai, ati Ṣafati ni Baṣani. 13 Ati awọn arakunrin wọn ti ile awọn baba wọn ni Mikaeli, ati Meṣullamu, ati Ṣeba, ati Jorai, ati Jakani, ati Sia, ati Heberi, meje. 14 Wọnyi li awọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi; 15 Adi, ọmọ Abdieli, ọmọ Guni, olori ile awọn baba wọn. 16 Nwọn si ngbe Gileadi ni Baṣani, ati ninu awọn ilu rẹ̀, ati ninu gbogbo igberiko Ṣaroni, li àgbegbe wọn. 17 Gbogbo wọnyi li a kà nipa itan-idile, li ọjọ Jotamu ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọba Israeli,

Àwọn ọmọ ogun àwọn ẹ̀yà ìhà ìlà oòrùn

18 Awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ninu awọn ọkunrin alagbara ti nwọn ngbé asà ati idà, ti nwọn si nfi ọrun tafà, ti nwọn si mòye ogun, jẹ ọkẹ meji enia o le ẹgbẹrinlelogún o di ogoji, ti o jade lọ si ogun na. 19 Nwọn si ba awọn ọmọ Hagari jagun, pẹlu Jeturi, ati Nefiṣi ati Nadabu. 20 A si ràn wọn lọwọ si wọn, a si fi awọn ọmọ Hagari le wọn lọwọ, ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu wọn: nitoriti nwọn kepè Ọlọrun li ogun na, on si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn: nitoriti nwọn gbẹkẹ wọn le e. 21 Nwọn si kó ẹran ọ̀sin wọn lọ; ibakasiẹ ẹgbãmẹ̃dọgbọ̀n ati àgutan ọkẹ mejila o le ẹgbãrun, ati kẹtẹkẹtẹ ẹgbã, ati enia ọkẹ marun. 22 Nitori ọ̀pọlọpọ li o ṣubu ti a pa, nitori lati ọdọ Ọlọrun li ogun na. Nwọn si joko ni ipò wọn titi di igbà ikolọ si ìgbekun.

Ìdajì Ẹ̀yà Manase tí ń gbé Ìhà Ìlà Oòrùn

23 Awọn ọmọkunrin àbọ ẹ̀ya Manasse joko ni ilẹ na: nwọn bi si i lati Baṣani titi de Baal-hermoni, ati Seniri, ati titi de òke Hermoni. 24 Wọnyi si li awọn olori ile awọn baba wọn, Eferi, ati Iṣi, ati Elieli, ati Asrieli, ati Jeremiah, ati Hodafiah, ati Jahdieli, awọn alagbara akọni ọkunrin, ọkunrin olokiki, ati olori ile awọn baba wọn.

A Kó Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Lẹ́rú Lọ

25 Nwọn si ṣẹ̀ si Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si ṣe àgbere tọ awọn ọlọrun enia ilẹ na lẹhin, ti Ọlọrun ti parun ni iwaju wọn. 26 Ọlọrun Israeli rú ẹmi Pulu ọba Assiria soke, ati ẹmi Tiglat-pilneseri ọba Assiria, on si kó wọn lọ, ani awọn ọmọ Rubeni ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, o si kó wọn wá si Hala, ati Habori, ati Hara, ati si odò Goṣani, titi di oni yi.

1 Kronika 6

Ìran Àwọn Olórí Àlùfáàa

1 AWỌN ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari. 2 Ati awọn Kohati; Amramu, Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli. 3 Ati awọn Amramu; Aaroni, ati Mose, ati Miriamu. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari. 4 Eleasari bi Finehasi, Finehasi si bi Abiṣua, 5 Abiṣua si bi Bukki, Bukki si bi Ussi, 6 Ussi si bi Serahiah, Serahiah si bi Meraioti, 7 Meraioti bi Amariah, Amariah si bi Ahitubu. 8 Ahitubu si bi Sadoku, Sadoku si bi Ahimaasi, 9 Ahimaasi si bi Asariah, Asariah si bi Johanani, 10 Johanani si bi Asariah (on na li ẹniti nṣiṣẹ alufa ni tempili ti Solomoni kọ́ ni Jerusalemu;) 11 Asariah si bi Amariah, Amariah si bi Ahitubu, 12 Ahitubu si bi Sadoki, Sadoki si bi Ṣallumu, 13 Ṣallumu si bi Hilkiah, Hilkiah si bi Asariah, 14 Asariah si bi Seraiah, Seraiah si bi Jehosadaki, 15 Jehosadaki si lọ si oko ẹrú, nigbati Oluwa kó Juda ati Jerusalemu lọ nipa ọwọ Nebukadnessari.

Àwọn Ìran Lefi Yòókù

16 Awọn ọmọ Lefi; Gersọmu, Kohati, ati Merari. 17 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Gerṣomu, Libni, ati Ṣimei. 18 Awọn ọmọ Kohati ni, Amramu, ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli. 19 Awọn ọmọ Merari; Mahli ati Muṣi. Wọnyi si ni idile awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi awọn baba wọn. 20 Ti Gerṣomu; Libni ọmọ rẹ̀, Jahati ọmọ rẹ̀, Simma ọmọ rẹ̀. 21 Joa ọmọ rẹ̀, Iddo ọmọ rẹ̀, Sera ọmọ rẹ̀, Jeaterai ọmọ rẹ̀. 22 Awọn ọmọ Kohati; Amminadabu ọmọ rẹ̀, Kora ọmọ rẹ̀, Assiri ọmọ rẹ̀. 23 Elkana ọmọ rẹ̀, ati Ebiasafu ọmọ rẹ̀, ati Assiri ọmọ rẹ̀, 24 Tahati ọmọ rẹ̀, Urieli ọmọ rẹ̀, Ussiah ọmọ rẹ̀, ati Ṣaulu ọmọ rẹ̀, 25 Ati awọn ọmọ Elkana; Amasai, ati Ahimoti. 26 Niti Elkana: awọn ọmọ Elkana; Sofai ọmọ rẹ̀, ati Nahati ọmọ rẹ̀, 27 Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀. 28 Awọn ọmọ Samueli; akọbi Faṣni, ati Abiah. 29 Awọn ọmọ Merari; Mahli, Libni, ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀, 30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀, Asaiah ọmọ rẹ̀,

Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Tẹmpili

31 Wọnyi si ni awọn ti Dafidi yàn ṣe olori iṣẹ orin ni ile Oluwa, lẹhin igbati apoti-ẹ̀ri Oluwa ti ni isimi. 32 Nwọn si nfi orin ṣe isin niwaju ibugbe agọ ajọ, titi Solomoni fi kọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu tan: nwọn si duro ti iṣẹ óye wọn gẹgẹ bi ipa wọn. 33 Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli, 34 Ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha, 35 Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai, 36 Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah, 37 Ọmọ Tahati, ọmọ Assiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, 38 Ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli. 39 Ati arakunrin rẹ̀ Asafu, ti o duro li ọwọ ọ̀tun rẹ̀, ani Asafu, ọmọ Berakiah, ọmọ Ṣimea, 40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah. 41 Ọmọ Etni, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah, 42 Ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei, 43 Ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Lefi. 44 Awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Merari duro lọwọ osi: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluku, 45 Ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah, 46 Ọmọ Amsi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣameri. 47 Ọmọ Mahli, ọmọ Muṣi ọmọ Merari, ọmọ Lefi, 48 Arakunrin wọn pẹlu, awọn ọmọ Lefi, li a yàn si oniruru iṣẹ gbogbo ti agọ ile Ọlọrun.

Ìran Aaroni

49 Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ. 50 Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀, 51 Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀, 52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀, 53 Sadoku ọmọ rẹ̀, Ahimaasi ọmọ rẹ̀.

Ibi tí àwọn Ọmọ Lefi ń gbé

54 Wọnyi si ni ibùgbe wọn gẹgẹ bi budo wọn li àgbegbe wọn, ti awọn ọmọ Aaroni, ti idile awọn ọmọ Kohati: nitori ti wọn ni ipin ikini. 55 Nwọn si fun wọn ni Hebroni ni ilẹ Juda, ati ìgberiko rẹ̀ yi i kakiri. 56 Ṣugbọn oko ilu na, ati ileto wọn, ni nwọn fun Kalebu ọmọ Jefunne. 57 Nwọn si fi ilu Juda fun awọn ọmọ Aaroni, ani Hebroni, ilu àbo ati Libna pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jattiri, ati Eṣtemoa, pẹlu ìgberiko wọn, 58 Ati Hileni pẹlu ìgberiko rẹ̀, Debiri pẹlu ìgberiko rẹ̀, 59 Ati Aṣani pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-ṣemeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀: 60 Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini; Geba pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Alemeti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anatoti pẹlu ìgberiko rẹ̀. Gbogbo ilu wọn ni idile wọn jẹ ilu mẹtala. 61 Ati fun awọn ọmọ Kohati, ti o kù ni idile ẹ̀ya na, li a fi keke fi ilu mẹwa fun, ninu àbọ ẹ̀ya, ani lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse. 62 Ati fun awọn ọmọ Gerṣomu ni idile wọn, lati inu ẹ̀ya Issakari, ati inu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati lati inu ẹ̀ya Manasse ni Baṣani, ilu mẹtala. 63 Fun awọn ọmọ Merari ni idile wọn li a fi keké fi ilu mejila fun, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati lati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni, 64 Awọn ọmọ Israeli fi ilu wọnyi fun awọn ọmọ Lefi pẹlu ìgberiko wọn. 65 Nwọn si fi keké fi ilu wọnyi ti a da orukọ wọn fun ni lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini. 66 Ati iyokù ninu idile awọn ọmọ Kohati ni ilu li àgbegbe wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu. 67 Nwọn si fi ninu ilu àbo fun wọn, Ṣekemu li òke Efraimu pẹlu ìgberiko rẹ̀; Geseri pẹlu ìgberiko rẹ̀, 68 Ati Jokneamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-horoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, 69 Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀: 70 Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù. 71 Awọn ọmọ Gerṣomu lati inu idile àbọ ẹ̀ya Manasse li a fi Golani ni Baṣani fun pẹlu ìgberiko rẹ̀; ati Aṣtaroti pẹlu ìgberiko rẹ̀, 72 Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀, 73 Ati Ramoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anemu pẹlu ìgberiko rẹ̀: 74 Ati lati inu ẹ̀ya Aṣeri; Maṣali pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Abdoni pẹlu ìgberiko rẹ̀. 75 Ati Hakoku pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Rehobu pẹlu ìgberiko rẹ̀: 76 Ati lati inu ẹ̀ya Naftali; Kedeṣi ni Galili pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Hammoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Kirjataimu pẹlu ìgberiko rẹ̀. 77 Fun iyokù awọn ọmọ Merari li a fi Rimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun, Tabori pẹlu ìgberiko rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni: 78 Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni, 79 Ati Kedemoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mefaati pẹlu ìgberiko rẹ̀: 80 Ati lati inu ẹ̀ya Gadi, Ramoti ni Gileadi pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mahanaimu pẹlu ìgberiko rẹ̀. 81 Ati Heṣboni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jaseri pẹlu ìgberiko rẹ̀.

1 Kronika 7

Àwọn Ìran Isakari

1 AWỌN ọmọ Issakari si ni, Tola, ati Pua, Jaṣubu, ati Ṣimroni, mẹrin. 2 Ati awọn ọmọ Tola; Ussi, ati Refaiah, ati Jerieli, ati Jamai, ati Jibsamu ati Samueli, awọn olori ile baba wọn, eyini ni ti Tola: akọni alagbara enia ni wọn ni iran wọn; iye awọn ẹniti o jẹ ẹgbã mọkanla o le ẹgbẹta li ọjọ Dafidi. 3 Awọn ọmọ Ussi: Israhiah ati awọn ọmọ Israhiah; Mikaeli, ati Obadiah, ati Joeli, ati Iṣiah, marun: gbogbo wọn li olori. 4 Ati pẹlu wọn, nipa iran wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun fun ogun, ẹgbã mejidilogun enia: nitoriti nwọn ni ọ̀pọlọpọ obinrin ati ọmọ ọkunrin. 5 Ati awọn arakunrin wọn ninu gbogbo idile Issakari jẹ akọni alagbara enia, ni kikaye gbogbo wọn nipa iran wọn, nwọn jẹ ẹgbamẹtalelogoji o le ẹgbẹrun.

Àwọn Ìran Bẹnjamini ati Dani

6 Awọn ọmọ Benjamini: Bela, ati Bekeri, ati Jediaeli, mẹta. 7 Awọn ọmọ Bela; Esboni, ati Ussi, ati Ussieli ati Jerimoti ati Iri, marun; awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia; a si kaye wọn nipa iran wọn si ẹgbãmọkanla enia o le mẹrinlelọgbọ̀n. 8 Awọn ọmọ Bekeri: Semira, ati Joaṣi, ati Elieseri, ati Elioeni, ati Omri, ati Jeremotu, ati Abiah, ati Anatoti, ati Alameti. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Bekeri. 9 Ati iye wọn, ni idile wọn nipa iran wọn, awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbawa o le igba. 10 Awọn ọmọ Jediaeli; Bilhani: ati awọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi, ati Benjamini, ati Ehudi, ati Kenaana, ati Setani, ati Tarṣiṣi ati Ahisahari. 11 Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun. 12 Ati Ṣuppimu, ati Huppimu, awọn ọmọ Iri, ati Huṣimu, awọn ọmọ Aheri.

Àwọn Ìran Nafutali

13 Awọn ọmọ Naftali: Jasieli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣallumu, awọn ọmọ Bilha.

Àwọn Ìran Manase

14 Awọn ọmọ Manasse; Aṣrieli, ti aya rẹ̀ bi: (ṣugbọn obinrin rẹ̀, ara Aramu, bi Makiri baba Gileadi: 15 Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin. 16 Maaka, obinrin Makiri, bi ọmọ, on si pè orukọ rẹ̀ ni Pereṣi: orukọ arakunrin rẹ̀ ni Ṣereṣi; ati awọn ọmọ rẹ̀ ni Ulamu ati Rakemu. 17 Awọn ọmọ Ulamu: Bedani. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse. 18 Arabinrin rẹ̀, Hammoleketi, bi Iṣodi, ati Abieseri, ati Mahala. 19 Ati awọn ọmọ Ṣemida ni, Ahiani, ati Ṣekemu, ati Likki, ati Aniamu.

Àwọn Ìran Efuraimu

20 Awọn ọmọ Efraimu: Ṣutela, ati Beredi ọmọ rẹ̀, ati Tahati, ọmọ rẹ̀, ati Elada, ọmọ rẹ̀, ati Tahati ọmọ rẹ̀. 21 Ati Sabadi ọmọ rẹ̀, ati Ṣutela ọmọ rẹ̀, ati Eseri, ati Eleadi, ẹniti awọn ọkunrin Gati, ti a bi ni ilẹ na, pa, nitori nwọn sọkalẹ wá lati kó ẹran ọ̀sin wọn lọ. 22 Efraimu baba wọn si ṣọ̀fọ li ọjọ pupọ, awọn arakunrin rẹ̀ si wá lati tù u ninu. 23 Nigbati o si wọle tọ̀ aya rẹ̀ lọ, o loyun o si bi ọmọ kan, on si pè orukọ rẹ̀ ni Beria, nitoriti ibi ba ile rẹ̀. 24 Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera. 25 Refa si ni ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Reṣefu pẹlu, ati Tela ọmọ rẹ̀, ati Tahani ọmọ rẹ̀. 26 Laadani ọmọ rẹ̀, Ammihudi ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀. 27 Nuni ọmọ rẹ̀, Joṣua ọmọ rẹ̀, 28 Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀: 29 Ati leti ilu awọn ọmọ Manasse, Betṣeani, ati ilu rẹ̀, Taanaki ati ilu rẹ̀, Megiddo ati ilu rẹ̀, Dori ati ilu rẹ̀. Ninu awọn wọnyi li awọn ọmọ Josefu, ọmọ Israeli, ngbe.

Àwọn Ìran Aṣeri

30 Awọn ọmọ Aṣeri: Imna, ati Iṣua, ati Iṣuai, ati Beria, ati Sera, arabinrin wọn. 31 Awọn ọmọ Beria: Heberi, ati Malkieli, ti iṣe baba Birsafiti. 32 Heberi si bi Jafleti, ati Ṣomeri, ati Hotamu, ati Ṣua, arabinrin wọn. 33 Ati awọn ọmọ Jafleti: Pasaki, ati Bimhali, ati Aṣfati. Wọnyi li awọn omọ Jafleti. 34 Awọn ọmọ Ṣameri: Ahi, ati Roga, Jehubba, ati Aramu. 35 Awọn ọmọ arakunrin rẹ̀ Helemu: Sofa, ati Imna, ati Ṣeleṣi, ati Amali. 36 Awọn ọmọ Sofa; Sua, ati Harneferi, ati Ṣuali, ati Beri, ati Imra, 37 Beseri, ati Hodi, ati Ṣamma, ati Ṣilṣa, ati Itrani, ati Beera. 38 Ati awọn ọmọ Jeteri: Jefunne, ati Pispa, ati Ara. 39 Ati awọn ọmọ Ulla: Ara, ati Hanieli, ati Resia. 40 Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.

1 Kronika 8

Àwọn Ìran Bẹnjamini

1 BENJAMINI si bi Bela, akọbi rẹ̀, Aṣbeli ekeji, ati Ahara ẹkẹta, 2 Noha ẹkẹrin, ati Rafa ẹkarun. 3 Awọn ọmọ Bela ni Addari, ati Gera, ati Abihudi, 4 Ati Abiṣua, ati Naamani, ati Ahoa, 5 Ati Gera, ati Ṣefufani, ati Huramu, 6 Wọnyi si li awọn ọmọ Ehudi: wọnyi li awọn olori baba wọn, ti nwọn ngbe Geba, nwọn si ko wọn lọ si Mahanati ni igbekun. 7 Ati Naamani, ati Ahiah, ati Gera, o si ko wọn kuro, o si bi Ussa ati Ahihudi. 8 Ṣaharaimu si bi ọmọ ni ilẹ Moabu; lẹhin igbati o ti ran wọn lọ tan; Huṣimu ati Baera si li awọn aya rẹ̀. 9 Hodeṣi, aya rẹ̀ si bi, Jobabu, ati Sibia, ati Meṣa, ati Malkama fun u, 10 Ati Jeusi, ati Ṣokia, ati Mirma. Wọnyi li awọn ọmọ rẹ̀, olori awọn baba. 11 Huṣimu si bi Ahitubu ati Elpaali fun u. 12 Awọn ọmọ Elpaali, Eberi, ati Miṣamu ati Ṣameri, ẹniti o kọ́ Ono ati Lodi pẹlu ilu wọn:

Àwọn Ará Bẹnjamini tí wọ́n wà ní Gati ati Aijalonii

13 Beria pẹlu, ati Ṣema, ti nwọn iṣe olori awọn baba awọn ara Ajaloni, awọn ti o le awọn ara Gati kuro. 14 Ati Ahio, Ṣaṣaki, Jerimotu, 15 Ati Sebadiah, ati Aradi, ati Aderi, 16 Ati Mikaeli, ati Ispa, ati Joha, ni awọn ọmọ Beria;

Àwọn Ará Bẹnjamini ní Jerusalẹmu

17 Ati Sobadiah, ati Meṣullamu, ati Heseki, ati Heberi. 18 Iṣmeri pẹlu, ati Jeslia, ati Jobabu, ni awọn ọmọ Elpaali. 19 Ati Jakimu, ati Sikri, ati Sabdi, 20 Ati Elienai, ati Siltai, ati Elieli, 21 Ati Adaiah, ati Beraiah, ati Ṣimrati ni awọn ọmọ Ṣimhi; 22 Ati Iṣpani, ati Eberi, ati Elieli, 23 Ati Abdoni, ati Sikri, ati Hanani, 24 Ati Hananiah, ati Elamu, ati Antotiah, 25 Ati Ifediah, ati Penueli, ni awọn ọmọ Ṣaṣaki; 26 Ati Samṣerai, ati Sehariah, ati Ataliah, 27 Ati Jaresiah, ati Eliah, ati Sikri, ni awọn ọmọ Jerohamu. 28 Wọnyi li olori awọn baba, nipa iran wọn, awọn olori. Awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.

Àwọn Ará Bẹnjamini tí Wọ́n Wà ní Gibeoni ati Jerusalẹmu

29 Ni Gibeoni ni baba Gibeoni si ngbe; orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka: 30 Ọmọ rẹ̀ akọbi si ni Abdoni, ati Suri, ati Kiṣi, ati Baali, ati Nadabu, 31 Ati Gedori, ati Ahio, ati Sakeri, 32 Mikloti si bi Ṣimea. Awọn wọnyi pẹlu si mba awọn arakunrin wọn gbe Jerusalemu, nwọn kọju si ara wọn.

Ìdílé Saulu Ọba

33 Neri si bi Kiṣi, ati Kiṣi si bi Saulu, ati Saulu si bi Jonatani, ati Milkiṣua, ati Abinadabu, ati Esbaali. 34 Ọmọ Jonatani si ni Meribaali; Meribaali si bi Mika. 35 Awọn ọmọ Mika ni Pitoni ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi. 36 Ahasi si bi Jehoadda; ati Jehoadda si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri: Simri si bi Mosa; 37 Mosa si bi Binea, Rafa ọmọ rẹ̀, Eleasari ọmọ rẹ̀, Aseli ọmọ rẹ̀: 38 Aseli si ni ọmọkunrin mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi, Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Seraiah, ati Obadiah, ati Hanani. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Aseli. 39 Awọn ọmọ Eṣeki arakunrin rẹ̀ si ni Ulamu akọbi rẹ̀, Jehuṣi ekeji, ati Elifeleti ẹkẹta. 40 Awọn ọmọ Ulamu si jẹ alagbara akọni ọkunrin, tafatafa, nwọn si li ọmọ pupọ ati ọmọ ọmọ adọjọ. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Benjamini.

1 Kronika 9

Àwọn tí wọ́n dé láti Oko Ẹrú Babilonii

1 A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 2 Awọn ti o tetekọ gbe ilẹ ini wọn, ati ilu wọn li awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu. 3 Ni Jerusalemu ni, ninu awọn ọmọ Juda, ati ninu awọn ọmọ Benjamini, ati ninu awọn ọmọ Efraimu, ati Manasse ngbe; 4 Utai ọmọ Ammihudi, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ninu awọn ọmọ Faresi ọmọ Juda. 5 Ati ninu awọn ara Ṣilo, Asaiah akọbi, ati awọn ọmọ rẹ̀. 6 Ati ninu awọn ọmọ Sera, Jegueli, ati awọn arakunrin wọn, ẹdẹgbẹrin o di mẹwa. 7 Ati ninu awọn ọmọ Benjamini; Sallu, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah, ọmọ Senua. 8 Ati Ibneiah ọmọ Jerohamu, ati Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri, ati Meṣullamu ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Regueli, ọmọ Ibniah; 9 Ati awọn arakunrin wọn, gẹgẹ bi idile wọn ẹgbẹrun o din mẹrinlelogoji. Gbogbo awọn ọkunrin wọnyi ni olori ninu awọn baba ni ile baba wọn.

Àwọn Àlùfáàa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu

10 Ati ninu awọn alufa; Jedaiah, ati Jehoiaribu ati Jakini, 11 Ati Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu olori ile Ọlọrun; 12 Ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkijah, ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Meṣillemiti, ọmọ Immeri; 13 Ati awọn arakunrin wọn olori ile baba wọn, ẹgbẹsan o din ogoji; awọn alagbara akọni ọkunrin fun iṣẹ ìsin ile Ọlọrun.

Àwọn Ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu

14 Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ninu awọn ọmọ Merari; 15 Ati Bakbakkari, Hereṣi, ati Galali, ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu; 16 Ati Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni, ati Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkanah, ti ngbe ileto awọn ara Netofa.

Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili tí wọn ń gbé Jerusalẹmu

17 Awọn adena si ni Ṣallumu, ati Akkubu, ati Talmoni, ati Ahimani, ati awọn arakunrin wọn; Ṣallumu li olori; 18 Titi di isisiyi awọn ti o duro li oju-ọ̀na ọba niha ilà-õrùn; adena ni wọn li ẹgbẹ awọn ọmọ Lefi. 19 Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na. 20 Ati Finehasi ọmọ Eleasari ni olori lori wọn ni igba atijọ, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. 21 Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia. 22 Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn. 23 Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ. 24 Ni igun mẹrẹrin ni awọn adena mbẹ, niha ilà-õrùn, ìwọ-õrún, ariwa ati gusu. 25 Ati awọn arakunrin wọn ngbe ileto wọn, lati ma wá pẹlu wọn ni ijọ ekeje lati igba de igba. 26 Nitoriti awọn ọmọ Lefi wọnyi jẹ awọn olori adena mẹrin, nwọn si wà ninu iṣẹ na, nwọn si wà lori iyara ati ibi iṣura ile Ọlọrun. 27 Nwọn a si ma sùn yi ile Ọlọrun ka, nitori ti nwọn ni itọju na, ati ṣiṣi rẹ̀ li orowurọ jẹ ti wọn.

Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù

28 Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye. 29 Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari. 30 Ati omiran ninu awọn ọmọ awọn alufa si fi turari ṣe ororo. 31 Ati Mattitiah, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi, ti iṣe akọbi Ṣallumu ọmọ Kora, li o nṣe alabojuto iṣẹ ohun ti a ndín. 32 Ati ninu awọn arakunrin wọn ninu awọn ọmọ Kohati li o nṣe itọju akara-ifihan, lati mã pese rẹ̀ li ọjọjọ isimi. 33 Wọnyi si li awọn akọrin, olori awọn baba awọn ọmọ Lefi, nwọn kò ni iṣẹ ninu iyara wọnni; nitori ti nwọn wà lẹnu iṣẹ wọn lọsan ati loru. 34 Awọn wọnyi ni olori baba awọn ọmọ Lefi, ni iran wọn, olori ni nwọn: awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.

Àwọn Baba Ńlá ati Àwọn Àtìrandíran Saulu Ọba

35 Ati ni Gibeoni ni baba Gibeoni ngbe, Jegieli, orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka. 36 Akọbi ọmọ rẹ̀ si ni Abdoni, ati Suri ati Kiṣi, ati Baali, ati Neri, ati Nadabu, 37 Ati Gedori, ati Ahio, ati Sekariah ati Mikloti. 38 Mikloti si bi Ṣimeamu. Awọn wọnyi si mba awọn arakunrin wọn gbe ni Jerusalemu, kọju si awọn arakunrin wọn. 39 Neri si bi Kiṣi, Kiṣi si bi Saulu, Saulu si bi Jonatani, ati Malkiṣua, ati Abinadabu, ati Eṣbaali. 40 Ati ọmọ Jonatani ni Merib-baali; Merib-baali si bi Mika. 41 Ati awọn ọmọ Mika ni Pitoni, ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi. 42 Ahasi si bi Jara; Jara si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri, Simri si bi Mosa, 43 Mosa si bi Binea, ati Refaiah ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀, Aseli ọmọ rẹ̀. 44 Aseli si bi ọmọ mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi; Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Ṣeariah, ati Obadiah ati Hanani. Wọnyi li awọn ọmọ Aseli.

1 Kronika 10

Ikú Saulu Ọba

1 AWỌN ara Filistia si ba Israeli jagun, awọn ọkunrin Israeli si sá niwaju awọn ara Filistia, nwọn fi ara pa, nwọn si ṣubu li òke Gilboa. 2 Awọn ara Filistia si lepa Saulu kikan, ati awọn ọmọ rẹ̀: awọn ara Filistia si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu. 3 Ogun na si le fun Saulu, awọn tafàtafà si ba a, on si damu nitori awọn tafàtafà. 4 Nigbana ni Saulu wi fun ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ pe, Fa idà rẹ yọ, ki o si fi gun mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má ba wá fi mi ṣẹsin. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nitori ẹ̀ru ba a gidigidi. Bẹ̃ni Saulu si mu idà, o si ṣubu le e. 5 Nigbati ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na pẹlu si ṣubu le idà rẹ̀, o si kú. 6 Bẹ̃ni Saulu kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹta, gbogbo ile rẹ̀ si kú ṣọkan. 7 Nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o wà ni pẹtẹlẹ ri pe nwọn sá, ati pe Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kú, nwọn fi ilu wọn silẹ, nwọn si sá: awọn ara Filistia si wá; nwọn si joko ninu wọn. 8 O si ṣe ni ijọ keji, nigbati awọn ara Filistia de lati wá bọ́ awọn okú li aṣọ, nwọn si ri Saulu pẹlu, ati awọn ọmọ rẹ̀ pe; nwọn ṣubu li òke Gilboa. 9 Nwọn si bọ́ ọ li aṣọ, nwọn si gbé ori rẹ̀ ati ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ si awọn ara Filistia yika, lati mu ihin lọ irò fun awọn ere wọn, ati fun awọn enia. 10 Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ sinu ile oriṣa wọn, nwọn si kan agbari rẹ̀ mọ ile Dagoni. 11 Nigbati gbogbo Jabeṣ-gileadi gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ara Filistia ti ṣe si Saulu, 12 Nwọn dide, gbogbo awọn ọkunrin ogun, nwọn si gbé okú Saulu lọ, ati okú awọn ọmọ rẹ̀, nwọn wá si Jabeṣi, nwọn si sìn egungun wọn labẹ igi oaku ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje. 13 Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere. 14 Kò si bère lọwọ Oluwa; nitorina li o ṣe pa a, o si yi ijọba na pada sọdọ Dafidi ọmọ Jesse.

1 Kronika 11

Dafidi Jọba lórí Israẹli ati Juda

1 NIGBANA ni gbogbo Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ Dafidi ni Hebroni, wipe, Kiyesi i, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe. 2 Ati pẹlu li atijọ, ani nigbati Saulu jẹ ọba, iwọ li o nmu Israeli jade ti o si nmu u wá ile: Oluwa Ọlọrun rẹ si wi fun ọ pe, Ki iwọ ki o bọ Israeli, enia mi, ki iwọ ki o si ṣe ọmọ-alade lori Israeli enia mi. 3 Nitorina ni gbogbo awọn agbagba Israeli ṣe tọ ọba wá ni Hebroni; Dafidi si ba wọn da majẹmu ni Hebroni niwaju Oluwa; nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba lori Israeli, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Samueli. 4 Ati Dafidi ati gbogbo Israeli jade lọ si Jerusalemu, ti iṣe Jebusi; awọn Jebusi ara ilẹ na ngbe ibẹ̀. 5 Awọn ara ilu Jebusi si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò gbọdọ wọ̀ ihinyi wa. Ṣugbọn Dafidi kó ilu odi Sioni ti iṣe ilu Dafidi. 6 Dafidi si wipe, Ẹnikẹni ti o ba tetekọ kọlù awọn ara Jebusi ni yio ṣe olori ati balogun. Bẹ̃ni Joabu ọmọ Seruiah si tetekọ gòke lọ, o si jẹ olori. 7 Dafidi si ngbe inu ilu odi, nitorina ni nwọn fi npè e ni ilu Dafidi. 8 O si kọ́ ilu na yikakiri; ani lati Millo yikakiri: Joabu si tun iyokù ilu na ṣe. 9 Bẹ̃ni Dafidi nga, o si npọ̀ si i: nitori ti Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu rẹ̀.

Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi tí Wọ́n Jẹ́ Olókìkí

10 Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli. 11 Eyi ni iye awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; Jaṣobeamu ọmọ Hakmoni, olori ninu awọn ọgbọ̀n balogun: on li o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia ti o pa lẹrikan. 12 Lẹhin rẹ̀ ni Eleaseri ọmọ Dodo, ara Ahohi, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn akọni mẹta. 13 On wà pẹlu Dafidi ni Pasdammimu, nigbati awọn ara Filistia ko ara wọn jọ lati jagun, nibiti ilẹ-bĩri kan wà ti o kún fun ọkà barli; awọn enia si salọ kuro niwaju awọn ara Filistia. 14 Nwọn si duro jẹ li ãrin ilẹ-bĩri na, nwọn si gbà a, nwọn si pa awọn ara Filistia; Oluwa si fi igbala nla gbà wọn. 15 Awọn mẹta ninu awọn ọgbọ̀n balogun si sọ̀kalẹ tọ̀ Dafidi lọ sibi apata na, ninu iho Adullamu; ogun ara Filistia si do li afonifoji Refaimu. 16 Dafidi si mbẹ ninu ilu odi nigbana, ẹgbẹ-ogun awọn ara Filistia si mbẹ ni Betlehemu li akoko na. 17 Dafidi si pòngbẹ, o si wipe, Emi iba ri ẹni fun mi mu ninu omi kanga Betlehemu ti mbẹ leti ẹnu-bodè! 18 Awọn mẹta na si la inu ogun awọn ara Filistia kọja, nwọn si fa omi jade lati inu kanga Betlehemu, lati ẹnu-bodè, nwọn gbé e, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá: Dafidi kò si fẹ mu u, ṣugbọn o tu u silẹ fun Oluwa, 19 O si wipe, Ki Ọlọrun mi má jẹ ki emi ki o ṣe eyi: ki emi ki o ha mu ẹ̀jẹ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwọn fi ẹmi wọn wewu? nipa ẹmi wọn ni nwọn fi mu u wá. Nitorina ni on kò ṣe fẹ mu u, nkan wọnyi li awọn akọni mẹta wọnyi ṣe. 20 Ati Abiṣai arakunrin Joabu, on li olori ninu awọn mẹta: nitoriti o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun o pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹta. 21 O ni ọla jù awọn mẹta ẹgbẹ ekeji lọ o si jẹ olori wọn: ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. 22 Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, o pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; on sọkalẹ, o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno. 23 O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o si sigbọnlẹ igbọnwọ marun ni gigun rẹ̀; ati li ọwọ ara Egipti na ni ọ̀kọ kan wà bi idubu igi awunṣọ; o si sọ̀kalẹ tọ ọ lọ pẹlu ọpa, a si já ọ̀kọ li ọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ rẹ̀ pa a. 24 Nkan wọnyi ni Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn akọni mẹta. 25 Kiyesi i, o li ọla jù awọn ọ̀gbọn lọ, ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. Dafidi si fi ṣe olori awọn igbimọ ile rẹ̀. 26 Awọn akọni ọkunrin ọmọ ogun rẹ̀ ni Asaheli arakunrin Joabu, Elhanani, ọmọ Dodo, ara Betlehemu. 27 Sammotu, ara Harori, Helesi, ara Peloni, 28 Ira, ọmọ Ikkeṣi, ara Tekoa, Abieseri ara Anatoti, 29 Sibbekai, ara Husa, Ilai, ara Ahohi, 30 Maharai, ara Netofa, Heledi ọmọ Baana, ara Netofa. 31 Itai ọmọ Ribai ti Gibea, ti awọn ọmọ Benjamini, Benaiah ara Piratoni, 32 Hurai ti odò Gaaṣi, Abieli ara Arbati, 33 Asmafeti ara Baharumi, Eliaba ara Ṣaalboni. 34 Awọn ọmọ Haṣemu ara Gisoni, Jonatani ọmọ Sage, ara Harari. 35 Ahihamu ọmọ Sakari, ara Harari, Elifali ọmọ Uri, 36 Heferi ara Mekerati, Ahijah ara Peloni, 37 Hesro ara Karmeli, Naari ọmọ Esbai, 38 Joeli arakunrin Natani, Mibhari ọmọ Haggeri, 39 Saleki ara Ammoni, Naharai ara Beroti, ẹniti nru ihamọra Joabu ọmọ Seruiah, 40 Ira ara Itri, Garobu ara Itri, 41 Uriah ara Heti, Sabadi ọmọ Ahalai, 42 Adina ọmọ Ṣisa ara Reubeni, olori awọn ara Reubeni, ati ọgbọ̀n enia pẹlu rẹ̀. 43 Hanani ọmọ Maaka, ati Jehoṣafati ara Mitini, 44 Ussia ara Aslerati, Ṣama ati Jegieli, awọn ọmọ Hotani, ara Aroeri, 45 Jediaeli ọmọ Simri, ati Joha arakunrin rẹ̀ ara Tisi, 46 Elieli ara Mahafi, ati Jeribai, ati Joṣafia, awọn ọmọ Elnaamu, ati Tima ara Moabu. 47 Elieli, ati Obedi, ati Jasieli ara Mesobah.

1 Kronika 12

Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ Jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Dafidi Ọba láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini

1 WỌNYI si li awọn ti o tọ̀ Dafidi wá si Siklagi, nigbati o fi ara rẹ̀ pamọ, nitori Saulu ọmọ Kiṣi: awọn wọnyi si wà ninu awọn akọni ti nṣe oluranlọwọ ogun na. 2 Nwọn le tafa, nwọn si le fi ọwọ ọtún ati ọwọ ọ̀si sọ okuta, ati fi ọrun tafa, ani ninu awọn arakunrin Saulu ti Benjamini. 3 Ahieseri ni olori, ati Joaṣi, awọn ọmọ Ṣemaa ara Gibea; ati Jesieli ati Peleti, awọn ọmọ Asmafeti; ati Beraka, ati Jehu ara Anatoti, 4 Ati Ismaiah ara Gibeoni, akọni ninu awọn ọgbọ̀n, ati lori ọgbọ̀n (enia) ati Jeremiah, ati Jahasieli, ati Johanani, ati Josabadi ara Gedera. 5 Elusai ati Jeremoti, ati Bealiah, ati Ṣemariah, ati Ṣefatiah ara Harofi, 6 Elkana, ati Jesiah, ati Asareelti ati Joeseri, ati Jaṣobeamu, awọn ara Kora, 7 Ati Joela, ati Sebadiah, awọn ọmọ Jerohamu ti Gedori.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Gadi

8 Ati ninu awọn ara Gadi, awọn ọkunrin akọni kan ya ara wọn sọdọ Dafidi ninu iho ni iju, awọn ọkunrin ogun ti o yẹ fun ija ti o le di asà on ọ̀kọ mu, oju awọn ẹniti o dabi oju kiniun, nwọn si yara bi agbọnrin lori awọn òke nla; 9 Eseri ekini, Obadiah ekeji, Eliobu ẹkẹta, 10 Miṣmanna ẹkẹrin, Jeremiah ẹkarun, 11 Attai ẹkẹfa, Elieli ekeje, 12 Johanani ẹkẹjọ, Elsabadi ẹkẹsan, 13 Jeremiah ẹkẹwa, Makbanai ẹkọkanla. 14 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gadi, awọn olori ogun: ẹniti o kere jù to fun ọgọrun enia, ati ẹniti o pọ̀ju to fun ẹgbẹrun. 15 Wọnyi li awọn ti o gòke odò Jordani li oṣù ekini, nigbati o kún bò gbogbo bèbe rẹ̀; nwọn si le gbogbo awọn ti o wà li afonifoji ninu ila-õrùn, ati niha iwọ-õrùn.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Bẹnjamini ati Ẹ̀yà Juda

16 Ninu awọn ọmọ Benjamini ati Juda si tọ Dafidi wá lori òke. 17 Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ. 18 Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Manase

19 Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀. 20 Bi on ti lọ si Siklagi, ninu awọn ẹya Manasse ya si ọdọ rẹ̀, Adna, ati Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli, ati Josabadi ati Elihu, ati Sittai, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ti iṣe ti Manasse. 21 Nwọn si ràn Dafidi lọwọ si ẹgbẹ ogun na; nitori gbogbo wọn ni akọni enia, nwọn si jẹ olori ninu awọn ọmọ-ogun. 22 Nitori li akokò na li ojojumọ ni nwọn ntọ Dafidi wá lati ran a lọwọ, titi o fi di ogun nla, gẹgẹ bi ogun Ọlọrun.

Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi

23 Eyi ni iye awọn enia na ti o hamọra tan fun ogun, ti nwọn si tọ̀ Dafidi wá si Hebroni, lati pa ijọba Saulu da si ọdọ rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. 24 Awọn ọmọ Juda ti ngbe asa ati ọ̀kọ, jẹ ẹgbãta enia o le ẹgbẹrin, ti o hamọra tan fun ogun. 25 Ninu awọn ọmọ Simeoni, akọni enia fun ogun ẹ̃dẹgbarin o le ọgọrun. 26 Ninu awọn ọmọ Lefi, ẹgbãji o le ẹgbẹta. 27 Jehoiada olori fun Aaroni, ẹgbẹ̃dogun enia o le ẽdẹgbẹrin si wà pẹlu rẹ̀. 28 Ati Sadoku, akọni ọdọmọkunrin, ati ninu ile baba rẹ̀ olori mejilelogun. 29 Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu. 30 Ati ninu awọn ọmọ Efraimu ẹgbãwa o le ẹgbẹrin, akọni ọkunrin, enia olorukọ ni nwọn ni ile baba wọn. 31 Ati àbọ ẹ̀ya Manasse ẹgbãsan, ti a yan nipa orukọ, lati lọ fi Dafidi jẹ ọba. 32 Ati ninu awọn ọmọ Issakari, ti o ni oye akoko, lati mọ̀ ohun ti Israeli iba ma ṣe; olori wọn jẹ igba; ati gbogbo awọn arakunrin wọn mbẹ ni ikawọ wọn. 33 Ninu ti Sebuluni, iru awọn ti o jade lọ si ogun ti o mọ̀ ogun iwé, pẹlu gbogbo ohun èlo ogun, ẹgbamẹ̃dọgbọn; ti nwọn kì ifi iye-meji tẹgun. 34 Ati ninu ti Naftali ẹgbẹrun olori ogun, ati pẹlu wọn ti awọn ti asa ati ọ̀kọ ẹgbã mejidilogun o le ẹgbẹrun. 35 Ati ninu awọn ọmọ Dani ti o mọ̀ ogun iwé, ẹgbã mẹtala o le ẹgbẹta. 36 Ati ninu ti Aṣeri, iru awọn ti njade lọ si ogun, ti o mọ̀ ogun iwé, ọkẹ meje. 37 Ati li apa keji odò Jordani, ninu ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati abọ ẹya Manasse, pẹlu gbogbo onirũru ohun elo ogun fun ogun ọ̀kọ, ọkẹ mẹfa. 38 Gbogbo awọn ọkunrin ogun wọnyi ti nwọn mọ̀ bi a iti itẹ ogun, nwọn fi ọkàn pipe wá si Hebroni, lati fi Dafidi jọba lori Israeli: gbogbo awọn iyokù ninu Israeli si jẹ oninu kan pẹlu lati fi Dafidi jẹ ọba. 39 Nibẹ, ni nwọn si wà pẹlu Dafidi ni ijọ mẹta, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nitoriti awọn ará wọn ti pèse fun wọn. 40 Pẹlupẹlu awọn ti o sunmọ wọn, ani titi de ọdọ Issakari, ati Sebuluni, ati Naftali, mu akara wá lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ibakasiẹ, ati lori ibãka, ati lori malu, ani onjẹ ti iyẹfun, eso ọ̀pọtọ, ati eso àjara gbigbẹ, ati ọti-waini, ati ororo, ati malu, ati agutan li ọ̀pọlọpọ: nitori ti ayọ̀ wà ni Israeli.

1 Kronika 13

A Gbé Àpótí Majẹmu kúrò ní Kiriati Jearimu

1 DAFIDI si ba awọn olori ogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun ati olukuluku olori gbèro. 2 Dafidi si wi fun gbogbo ijọ Israeli pe, Bi o ba dara loju nyin, bi o ba si ti ọwọ Oluwa Ọlọrun wa wá, jẹ ki a ranṣẹ kiri sọdọ awọn arakunrin wa ni ibi gbogbo, ti o kù ni gbogbo ilẹ Israeli, ati pẹlu wọn si alufa ati awọn ọmọ Lefi ti mbẹ ni ilu agbegbe wọn, ki nwọn ki o le ko ara wọn jọ sọdọ wa: 3 Ẹ jẹ ki a si tun mu apoti ẹri Ọlọrun wa wa si ọdọ wa: nitoriti awa kò ṣafẹri rẹ̀ li ọjọ Saulu. 4 Gbogbo ijọ na si wipe, ẹ jẹ ki a ṣe bẹ̃: nitori ti nkan na tọ loju gbogbo enia. 5 Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá. 6 Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun. 7 Nwọn si gbé apoti ẹri Ọlọrun ka kẹkẹ́ titun lati inu ile Abinadabu wá, ati Ussa ati Ahio ntọ́ kẹkẹ́ na. 8 Ati Dafidi ati gbogbo Israeli fi gbogbo agbara wọn ṣire niwaju Ọlọrun, pẹlu orin, ati pẹlu duru, ati pẹlu psalteri, ati pẹlu timbreli, ati pẹlu simbali, ati pẹlu ipè. 9 Nigbati nwọn si de ilẹ ipaka Kidroni, Ussa nà ọwọ rẹ̀ lati di apoti ẹri na mu; nitoriti awọn malu kọsẹ. 10 Ibinu Oluwa si ru si Ussa, o si lù, nibẹ li o si kú niwaju Ọlọrun. 11 Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni. 12 Dafidi si bẹ̀ru Ọlọrun li ọjọ na wipe, Emi o ha ṣe mu apoti ẹri Ọlọrun wá sọdọ mi? 13 Bẹ̃ni Dafidi kò mu apoti ẹri na bọ̀ si ọdọ ara rẹ̀ si ilu Dafidi, ṣugbọn o gbé e ya si ile Obed-Edomu ara Gitti. 14 Apoti ẹri Ọlọrun si ba awọn ara ile Obed-Edomu gbe ni ile rẹ̀ li oṣu mẹta. Oluwa si bukún ile Obed-Edomu ati ohun gbogbo ti o ni.

1 Kronika 14

Akitiyan Dafidi ní Jerusalẹmu

1 HIRAMU ọba Tire si ran onṣẹ si Dafidi, ati igi Kedari, pẹlu awọn ọmọle ati gbẹnagbẹna, lati kọ́le fun u. 2 Dafidi si woye pe, Oluwa ti fi idi on joko li ọba lori Israeli, nitori a gbé ijọba rẹ̀ ga nitori ti awọn enia rẹ̀, Israeli. 3 Dafidi si mu awọn aya si i ni Jerusalemu: Dafidi si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin si i. 4 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ti o ni ni Jerusalemu; Ṣammua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni, 5 Ati Ibhari, ati Eliṣua, ati Elpaleti, 6 Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia, 7 Ati Eliṣama, ati Beeliada, ati Elifaleti.

Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Filistia

8 Nigbati awọn ara Filistia si gbọ́ pe, a fi ororo yan Dafidi li ọba lori gbogbo Israeli, gbogbo awọn ara Filistia gòke lọ iwá Dafidi: Dafidi si gbọ́, o si jade tọ̀ wọn. 9 Awọn ara Filistia si wá, nwọn si tẹ ara wọn ni afonifoji Refaimu. 10 Dafidi si bere lọdọ Ọlọrun wipe, Ki emi ki o gòke tọ awọn ara Filistia lọ? Iwọ o ha fi wọn le mi lọwọ? Oluwa si wi fun u pe, Gòke lọ, emi o si fi wọn le ọ lọwọ. 11 Bẹ̃ni nwọn gòke lọ si Baal-perasimu; Dafidi si kọlù wọn nibẹ. Dafidi si wipe, Ọlọrun ti ti ọwọ mi yà lu awọn ọta mi bi yiya omi: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ na ni Baal-perasimu. 12 Nwọn si fi awọn orisa wọn silẹ nibẹ, Dafidi si wipe, ki a fi iná sun wọn. 13 Awọn ara Filistia si tun tẹ ara wọn kakiri ni afonifoji. 14 Nitorina ni Dafidi tun bère lọwọ Ọlọrun: Ọlọrun si wi fun u pe, Máṣe gòke tọ̀ wọn; yipada kuro lọdọ wọn, ki o si ja lu wọn niwaju igi mulberi. 15 Yio si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lòke igi mulberi, nigbana ni ki iwọ ki o gbogun jade: nitori Ọlọrun jade ṣaju rẹ lọ lati kọlù ogun awọn ara Filistia. 16 Dafidi si ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun u: nwọn si kọlù ogun awọn ara Filistia lati Gibeoni titi de Gaseri. 17 Okiki Dafidi si kan yi gbogbo ilẹ ka. Oluwa si mu ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o ba gbogbo orilẹ-ède.

1 Kronika 15

Ìmúra láti Gbé Àpótí Majẹmu Pada

1 DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u. 2 Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai. 3 Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u. 4 Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ. 5 Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa: 6 Ninu awọn ọmọ Merari; Asaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba o le ogun: 7 Ninu awọn ọmọ Gerṣomu; Joeli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ãdoje: 8 Ninu awọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba. 9 Ninu awọn ọmọ Hebroni; Elieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọrin: 10 Ninu awọn ọmọ Ussieli; Aminadabu olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ mejilelãdọfa. 11 Dafidi si ranṣẹ pè Sadoku ati Abiatari awọn alufa; ati awọn ọmọ Lefi, Urieli, Asaiah, ati Joeli, Ṣemaiah, ati Elieli, ati Aminadabu; 12 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi: ẹ ya ara nyin si mimọ́, ẹnyin ati awọn arakunrin nyin, ki ẹnyin ki o le gbé apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke lọ si ibi ti mo ti pèse fun u. 13 Nitoriti ẹnyin kò rù u li akọṣe, ni Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe ẹ̀ya si wa li ara, nitori awa kò wá a bi o ti yẹ. 14 Bẹ̃ li awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ya ara wọn si mimọ́ lati gbe apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke wá. 15 Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn. 16 Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke. 17 Bẹ̃ li awọn ọmọ Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; ati ninu awọn arakunrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah; ati ninu awọn ọmọ Merari arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah; 18 Ati pẹlu wọn awọn arakunrin wọn li ọwọ́ keji; Sekariah, Beni, ati Jaasieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Unni, Eliabu, ati Benaiah, ati Maaseiah, ati Obed-Edomu, ati Jeieli awọn adena. 19 Awọn akọrin si ni Hemani, Asafu, ati Etani, ti awọn ti kimbali ti ndun kikan; 20 Ati Sekariah, ati Asieli, ati Ṣemiramotu, ati Jelieli, ati Unni, ati Eliabu, ati Maaseiah, ati Benaiah, ti awọn ti psaltiri olohùn òke; 21 Ati Mattitiah, ati Elifeleti, ati Mikneiah, lati fi duru olokun mẹjọ ṣaju orin. 22 Ati Kenaniah, olori awọn ọmọ Lefi ni ọ̀ga orin: on ni nkọni li orin, nitoriti o moye rẹ̀. 23 Ati Berekiah, ati Elkana li awọn adena fun apoti ẹri na. 24 Ati Ṣebaniah, ati Jehoṣafati, ati Netaneeli, ati Amasai, ati Sekariah, ati Benaiah, ati Elieseri, awọn alufa, li o nfun ipè niwaju apoti ẹri Ọlọrun: ati Obed-Edomu, ati Jehiah li awọn adena fun apoti ẹri na.

Gbígbé Àpótí Majẹmu Lọ sí Jerusalẹmu

25 Bẹ̃ni Dafidi ati awọn agbagba Israeli, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun, lọ lati gbe apoti ẹri majẹmu Oluwa jade ti ile Obed-Edomu gòke wá pẹlu ayọ̀. 26 O si ṣe, nigbati Ọlọrun ràn awọn ọmọ Lefi lọwọ ti o rù apoti ẹri majẹmu Oluwa, ni nwọn fi malu meje ati àgbo meje rubọ. 27 Dafidi si wọ̀ aṣọ igunwa ọ̀gbọ daradara, ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti nrù apoti ẹri na, ati awọn akọrin, ati Kenaniah olori orin pẹlu awọn akọrin: efodu ọ̀gbọ si wà lara Dafidi. 28 Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan. 29 O si ṣe bi apoti ẹri majẹmu Oluwa na ti de ilu Dafidi ni Mikali ọmọ Saulu obinrin yọju wode ni fèrese, o ri Dafidi ọba njó, o si nṣire; o si kẹgan rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.

1 Kronika 16

1 BẸ̀NI nwọn mu apoti ẹri Ọlọrun wá, nwọn si fi si arin agọ na ti Dafidi pa fun u: nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju Ọlọrun, 2 Nigbati Dafidi si ti pari riru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia tan, o sure fun awọn enia li orukọ Oluwa. 3 O si fi fun gbogbo enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin fun olukulùku iṣu akara kan, ati ekiri ẹran kan, ati akara didùn kan. 4 O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli: 5 Asafu ni olori, ati atẹle rẹ̀ ni Sekariah, Jeieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Mattitiah, ati Eliabu, ati Benaiah, ati Obed-Edomu: ati Jeieli pẹlu psalteri ati pẹlu duru; ṣugbọn Asafu li o nlù kimbali kikan; 6 Benaiah pẹlu ati Jahasieli awọn alufa pẹlu ipè nigbagbogbo niwaju apoti ẹri ti majẹmu Ọlọrun. 7 Li ọjọ na ni Dafidi kọ́ fi orin mimọ́ yi le Asafu lọwọ lati dupẹ lọwọ Oluwa.

Orin Ìyìn

8 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, ẹ pè orukọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. 9 Ẹ kọrin si i, ẹ kọ́ orin mimọ́ si i, ẹ ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀. 10 Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki ọkàn awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. 11 Ẹ ma wá Oluwa, ati ipa rẹ̀, ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. 12 Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe, iṣẹ àmi rẹ̀, ati idajọ ẹnu rẹ̀; 13 Ẹnyin iru-ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu ayanfẹ rẹ̀. 14 On ni Oluwa Ọlọrun wa, idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. 15 Ẹ ma ṣe iranti majẹmu rẹ̀ titi lai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran; 16 Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; 17 A si tẹnumọ eyi li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye: 18 Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin. 19 Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀. 20 Nwọn si nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ati lati ijọba kan de ọdọ enia miran; 21 On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ìwọsi, nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn, 22 Wipe, Ẹ má ṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi, ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi. 23 Ẹ kọrin titun si Oluwa gbogbo aiye; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. 24 Ẹ sọ̀rọ ogo rẹ̀ ninu awọn keferi; ati iṣẹ-iyanu rẹ̀ ninu gbogbo enia. 25 Nitori titobi li Oluwa, o si ni iyìn gidigidi: on li o si ni ibẹ̀ru jù gbogbo oriṣa lọ. 26 Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun. 27 Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀. 28 Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa. 29 Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. 30 Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi. 31 Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba. 32 Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀. 33 Nigbana ni awọn igi igbo yio ma ho niwaju Oluwa, nitori ti o mbọ wá ṣe idajọ aiye. 34 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. 35 Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ. 36 Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.

Ìjọ́sìn ní Gibeoni ati ní Jerusalẹmu

37 Bẹ̃ li o fi Asafu ati awọn arakunrin rẹ̀ silẹ nibẹ niwaju apoti ẹri majẹmu Oluwa lati ma jọsìn niwaju apoti ẹri na nigbagbogbo, bi iṣẹ ojojumọ ti nfẹ. 38 Ati Obed-Edomu pẹlu awọn arakunrin wọn, enia mejidilãdọrin; ati Obed-Edomu ọmọ Jedutuni, ati Hosa lati ma ṣe adena: 39 Sadoku alufa, ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn alufa, niwaju agọ Oluwa, ni ibi giga ti o wà ni Gibeoni, 40 Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli; 41 Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni, ati awọn iyokù ti a yàn, ti a si pe li orukọ, lati ma fi ìyin fun Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai; 42 Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni pẹlu ipè ati kimbali fun awọn ti yio ma pariwo, ati pẹlu ohun èlo orin Ọlọrun. Awọn ọmọ Jedutuni li awọn adena. 43 Gbogbo awọn enia si lọ olukuluku si ile rẹ̀: Dafidi yipada lati sure fun ile rẹ̀.

1 Kronika 17

Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ fún Dafidi

1 O SI ṣe, bi Dafidi ti joko ninu ile rẹ̀, ni Dafidi sọ fun Natani woli pe, Wò o, emi ngbe inu ile kedari, ṣugbọn apoti ẹri majẹmu Oluwa ngbe abẹ aṣọ-tita. 2 Nigbana ni Natani wi fun Dafidi pe, Ṣe ohun gbogbo ti mbẹ ni inu rẹ; nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ. 3 O si ṣe li oru kanna ni ọ̀rọ Ọlọrun tọ Natani wá, wipe, 4 Lọ, si sọ fun Dafidi iranṣẹ mi pe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun mi lati ma gbe. 5 Nitori emi kò ti igbe inu ile lati ọjọ ti mo ti mu Israeli gòke wá titi fi di oni yi; ṣugbọn emi nlọ lati agọ de agọ, ati lati ibugbe kan de keji. 6 Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi? 7 Njẹ nitorina bayi ni iwọ o wi fun Dafidi iranṣẹ mi, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Emi mu ọ kuro ni pápá oko-tutu, ani kuro lati ma tọ agutan lẹhin, ki iwọ ki o le ma ṣe olori awọn enia mi Israeli. 8 Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye. 9 Emi o si yan ibi kan fun Israeli awọn enia mi, emi o si gbìn wọn, ki nwọn le má gbe ipò wọn, a kì yio si ṣì wọn mọ; bẹ̃ni ọmọ buburu kì yio yọ wọn lẹnu mọ, bi ti atijọ; 10 Ati bi igba ti emi ti fi enia jẹ onidajọ lori awọn enia mi Israeli. Ati pẹlu emi o ṣẹgun gbogbo awọn ọta rẹ. Pẹlupẹlu mo ti sọ fun ọ pe, Oluwa yio kọle kan fun ọ. 11 Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ. 12 On o kọ́ ile fun mi, emi o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai. 13 Emi o jẹ baba fun u, on o si jẹ ọmọ fun mi; emi kì yio si gbà ãnu mi kuro lọdọ rẹ̀, bi mo ti gbà a lọwọ ẹniti o ti wà ṣaju rẹ: 14 Ṣugbọn emi o fi idi rẹ̀ kalẹ ninu ile mi ati ninu ijọba mi lailai, a o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai. 15 Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani sọ fun Dafidi.

Adura Ọpẹ́ tí Dafidi Gbà

16 Dafidi ọba si wá, o si joko niwaju Oluwa, o si wipe, Tali emi Oluwa Ọlọrun, ati kini ile mi, ti iwọ si mu mi de ihinyi? 17 Ohun kekere si li eyi li oju rẹ, Ọlọrun: iwọ si ti sọ pẹlu sipa ile iranṣẹ rẹ fun akokò jijin ti mbọ, o si ka mi si bi iṣe enia giga, Oluwa Ọlọrun. 18 Kini Dafidi le tun ma sọ pẹlu fun ọ niti ọlá ti a bù fun iranṣẹ rẹ? iwọ sa mọ̀ iranṣẹ rẹ. 19 Oluwa, nitoriti iranṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi ti inu rẹ, ni iwọ ti ṣe gbogbo ohun nlanla yi, ni sisọ gbogbo nkan nla wọnyi di mimọ̀. 20 Oluwa, kò si ẹniti o dabi rẹ bẹ̃ni kò si Ọlọrun miran lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa ti fi eti wa gbọ́. 21 Orilẹ-ède kan wo li o wà li aiye ti o dabi enia rẹ, Israeli, ti Ọlọrun lọ irapada lati ṣe enia on tikararẹ, lati ṣe orukọ fun ara rẹ nipa ohun ti o tobi ti o si lẹ̀ru, ni lile awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti rapada lati Egipti jade wá? 22 Nitori awọn enia rẹ Israeli li o ti ṣe li enia rẹ titi lai; iwọ Oluwa, si di Ọlọrun wọn. 23 Njẹ nisisiyi, Oluwa! jẹ ki ọ̀rọ ti iwọ ti sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti ile rẹ̀ ki o fi idi mulẹ lailai, ki iwọ ki o si ṣe bi iwọ ti wi. 24 Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ. 25 Nitori iwọ, Ọlọrun mi, ti ṣi iranṣẹ rẹ li eti pe, Iwọ o kọ́ ile kan fun u: nitorina ni iranṣẹ rẹ ri i lati gbadua niwaju rẹ. 26 Njẹ nisisiyi Oluwa, Iwọ li Ọlọrun, iwọ si ti sọ ọ̀rọ ore yi fun iranṣẹ rẹ; 27 Njẹ nisisiyi jẹ ki o wù ọ lati bukún ile iranṣẹ rẹ, ki o le ma wà niwaju rẹ lailai: nitori iwọ Oluwa, ẹniti o sure fun, ire ni o si ma jẹ lailai.

1 Kronika 18

Àwọn Ogun tí Dafidi Jà ní Àjàṣẹ́gun

1 O SI ṣe lẹhin eyi, ni Dafidi kọlu awọn ara Filistia, o si ṣẹ́ wọn, o si gbà Gati ati ilu rẹ̀ lọwọ awọn ara Filistia. 2 O si kọlu Moabu, awọn ara Moabu si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. 3 Dafidi si kọlu Hadareseri ọba Soba ni Hamati bi o ti nlọ lati fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ leti odò Euferate. 4 Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ́, ati ẹ̃dẹgbarun ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa ẹlẹsẹ lọwọ rẹ̀: Dafidi si ja iṣan ẹsẹ gbogbo awọn ẹṣin kẹkẹ́ na, ṣugbọn o pa ọgọrun ẹṣin kẹkẹ́ mọ ninu wọn. 5 Nigbati awọn ara Siria ti Damasku wá lati ran Hadareseri ọba Soba lọwọ, Dafidi pa ẹgbã mọkanla enia ninu awọn ara Siria. 6 Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ. 7 Dafidi si gbà awọn asa wura ti mbẹ lara awọn iranṣẹ Hadareseri, o si mu wọn wá si Jerusalemu. 8 Lati Tibhati pẹlu ati lati Kuni, ilu Hadareseri ni Dafidi ko ọ̀pọlọpọ idẹ, eyiti Solomoni fi ṣe okun idẹ, ọwọn wọnni, ati ohun elo idẹ wọnni. 9 Nigbati Tou ọba Hamati gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadareseri ọba Soba. 10 O ran Hadoramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba lati ki i ati lati yọ̀ fun u, nitoriti o ti ba Hadareseri jà o si ti ṣẹgun rẹ̀; (nitori Tou ti jẹ ọta Hadareseri) o si ni oniruru ohun elo wura ati ti fadakà ati idẹ pẹ̀lu rẹ̀. 11 Awọn pẹlu ni Dafidi yà si mimọ́ fun Oluwa pẹlu fadakà ati wura ti o ko lati ọdọ gbogbo orilẹ-ède wọnni wá; lati Edomu, ati lati Moabu, ati lati ọdọ awọn ọmọ Ammoni, ati lati ọdọ awọn ara Filistia, ati lati Amaleki wá, 12 Pẹlupẹlu Abiṣai ọmọ Seruiah pa ẹgbãsan ninu awọn ara Edomu li afonifoji Iyọ̀. 13 O si fi ẹgbẹ-ogun si Edomu: ati gbogbo awọn ara Edomu si di iranṣẹ Dafidi. Bayi li Oluwa ngbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ. 14 Bẹ̃ ni Dafidi jọba lori gbogbo Israeli, o si ṣe idajọ ati otitọ larin awọn enia rẹ̀. 15 Joabu ọmọ Seruiah si wà lori ogun; ati Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọwe-iranti. 16 Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Abimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; ati Ṣafṣa ni akọwe; 17 Benaiah ọmọ Jehoiada li o si wà lori awọn Kereti ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si li olori lọdọ ọba.

1 Kronika 19

Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni ati Àwọn Ará Siria

1 O SI ṣe lẹhin eyi, ni Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni kú, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. 2 Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu. 3 Ṣugbọn awọn ijoye awọn ọmọ Ammoni wi fun Hanuni pe, Iwọ rò pe Dafidi bu ọlá fun baba rẹ nitori ti o ran awọn olutunu si ọ? Kò ṣepe awọn iranṣẹ rẹ̀ wá si ọdọ rẹ lati rin wò, ati lati bi ṣubu ati lati ṣe ami ilẹ na? 4 Nitorina Hanuni kó awọn iranṣẹ Dafidi, o si fa irungbọn wọn, o si ké agbáda wọn sunmọ ibadi wọn, o ran wọn lọ. 5 Nigbana ni awọn kan lọ, nwọn si sọ fun Dafidi bi a ti ṣe awọn ọkunrin na: on si ranṣẹ lọ ipade wọn: nitori oju tì awọn ọkunrin na gidigidi. Ọba si wipe, Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọn nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ si pada wá. 6 Nigbati awọn ọmọ Ammoni ri pe nwọn ti ba ara wọn jẹ lọdọ Dafidi, Hanuni ati awọn ọmọ Ammoni ran ẹgbẹrun talenti fadakà lati bẹ̀wẹ kẹkẹ́ ati ẹlẹsin lati Siria ni Mesopotamia wá, ati lati Siria-Maaka wá, ati lati Soba wá. 7 Bẹ̃ni nwọn bẹwẹ ẹgbã mẹrindilogun kẹkẹ́ ati ọba Maaka ati awọn enia rẹ̀; nwọn si wá nwọn si do niwaju Medeba. Awọn ọmọ Ammoni si ko ara wọn jọ lati ilu wọn, nwọn si wá si ogun. 8 Nigbati Dafidi gbọ́, o ran Joabu ati gbogbo ogun awọn akọni enia. 9 Awọn ọmọ Ammoni si jade wá, nwọn si tẹ ogun niwaju ẹnu-ibode ilu na: awọn ọba ti o wá si wà li ọtọ̀ ni igbẹ. 10 Nigbati Joabu ri pe a doju ija kọ on, niwaju ati lẹhin, o yàn ninu gbogbo ãyo Israeli, o si tẹ ogun wọn si awọn ara Siria. 11 O si fi iyokù awọn enia le Abiṣai arakunrin rẹ̀ lọwọ, nwọn si tẹ ogun si awọn ọmọ Ammoni. 12 On si wipe, Bi awọn ara Siria ba le jù fun mi, nigbana ni iwọ o ran mi lọwọ: ṣugbọn bi awọn ọmọ Ammoni ba le jù fun ọ, nigbana li emi o ràn ọ lọwọ. 13 Ṣe giri ki o si jẹ ki a huwa akọni fun enia wa ati fun ilu Ọlọrun wa: ki Oluwa ki o si ṣe eyi ti o dara loju rẹ̀. 14 Bẹ̃ni Joabu ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀ sún siwaju awọn ara Siria si ibi ija: nwọn si sá niwaju rẹ̀. 15 Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn pẹlu sá niwaju Abiṣai arakunrin rẹ̀, nwọn si wọ̀ ilu lọ. Nigbana ni Joabu wá si Jerusalemu. 16 Nigbati awọn ara Siria ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ran onṣẹ, nwọn si fà awọn ara Siria ti mbẹ lòke odò: Ṣofaki olori ogun Hadareseri sì ṣiwaju wọn. 17 A si sọ fun Dafidi; on si ko gbogbo Israeli jọ, o si gòke odò Jordani o si yọ si wọn, o si tẹ ogun si wọn. Bẹ̃ni nigbati Dafidi tẹ ogun si awọn ara Siria, nwọn ba a jà. 18 Ṣugbọn awọn ara Siria sá niwaju Israeli, Dafidi si pa ẹ̃dẹgbarin enia ninu awọn ara Siria ti o wà ninu kẹkẹ́, ati ọkẹ-meji ẹlẹsẹ, o si pa Ṣofaki olori ogun na. 19 Nigbati awọn iranṣẹ Hadareseri ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ba Dafidi làja, nwọn si nsìn i: bẹ̃ni awọn ara Siria kò jẹ ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.

1 Kronika 20

Dafidi Ṣẹgun Raba

1 O SI ṣe lẹhin igbati ọdun yipo, li akokò ti awọn ọba lọ si ogun; Joabu si gbé agbara ogun jade, o si ba ilu awọn ọmọ Ammoni jẹ, nwọn si wá, nwọn si do tì Rabba. Ṣugbọn Dafidi duro ni Jerusalemu. Joabu si kọlù Rabba o si pa a run. 2 Dafidi si gbà ade ọba wọn kuro lori rẹ̀, o si ri i pe o wọ̀n talenti wura kan, okuta iyebiye si wà lara rẹ̀; a si fi de Dafidi li ori: o si kó ikogun pipọpipọ lati inu ilu na wá. 3 O si kó awọn enia ti o wà nibẹ jade wá, o si fi ayùn ati irin mimu ati ãke ké wọn. Aní bayi ni Dafidi ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Ati Dafidi ati gbogbo awọn enia pada bọ̀ si Jerusalemu.

Bíbá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun

4 O si ṣe lẹhin eyi li ogun si de ni Geseri pẹlu awọn ara Filistia; li akokò na ni Sibbekai ara Huṣa pa Sippai, ti inu awọn ọmọ òmiran: a si tẹ ori wọn ba. 5 Ogun si tun wà pẹlu awọn ara Filistia; Elhanani ọmọ Jairi si pa Lahamu arakunrin Goliati ara Gati, igi ọ̀kọ rẹ̀ si dabi ìti awunṣọ. 6 Ogun si tun wà ni Gati, nibiti ọkunrin gigun kan gbe wà, ika ati ọmọ-ẹsẹ ẹniti o jẹ mẹrinlelogun, mẹfa li ọwọ kọkan, ati mẹfa li ẹṣẹ kọkan, a si bi i pẹlu fun òmiran. 7 Ṣugbọn nigbati o pe Israeli ni ija, Jonatani ọmọ Ṣimea arakunrin Dafidi pa a. 8 Awọn wọnyi li a bi fun òmiran ni Gati; nwọn si tipa ọwọ Dafidi ṣubu, ati ipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀.

1 Kronika 21

Dafidi Ṣe Ètò Ìkànìyàn

1 SATANI si duro tì Israeli, o si tì Dafidi lati ka iye Israeli. 2 Dafidi si wi fun Joabu ati awọn olori enia pe, Lọ ikaye Israeli lati Beerṣeba titi de Dani; ki o si mu iye wọn fun mi wá, ki emi ki o le mọ̀ iye wọn. 3 Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi. 4 Ṣugbọn ọ̀rọ ọba bori ti Joabu, nitorina Joabu jade lọ, o si la gbogbo Israeli ja, o si de Jerusalemu. 5 Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà. 6 Ṣugbọn Lefi ati Benjamini ni kò kà pẹlu wọn: nitori ọ̀rọ ọba jẹ irira fun Joabu. 7 Nkan yi si buru loju Ọlọrun; o si kọlù Israeli. 8 Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi ti ṣẹ̀ gidigidi ni ṣiṣe nkan yi: ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ kuro; nitoriti mo hùwa wère gidigidi. 9 Oluwa si wi fun Gadi, ariran Dafidi pe, 10 Lọ ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, mo fi nkan mẹta lọ̀ ọ: yàn ọkan ninu wọn ki emi ki o le ṣe e si ọ. 11 Bẹ̃ni Gadi tọ Dafidi wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, yan fun ara rẹ, 12 Yala ọdun mẹta iyan, tabi iparun li oṣù mẹta niwaju awọn ọta rẹ, ti idà awọn ọta rẹ nle ọ ba; tabi idà Oluwa, ni ijọ mẹta, ani ajakalẹ àrun ni ilẹ na, ti angeli Oluwa o ma pani ja gbogbo àgbegbe Israeli. Njẹ nisisiyi rò o wò, esi wo ni emi o mu pada tọ̀ ẹniti o ran mi. 13 Dafidi si wi fun Gadi pe, iyọnu nla ba mi: jẹ ki emi ki o ṣubu si ọwọ Oluwa nisisiyi: nitori ãnu rẹ̀ pọ̀; ṣugbọn má jẹ ki emi ṣubu si ọwọ ẹnia. 14 Bẹ̃ li Oluwa ran ajakalẹ arun si Israeli: awọn ti o ṣubu ni Israeli jẹ ẹgbã marundilogoji enia. 15 Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi. 16 Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ. 17 Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn. 18 Nigbana ni angeli Oluwa na paṣẹ fun Gadi lati sọ fun Dafidi pe, ki Dafidi ki o gòke lọ ki o si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa, ni ilẹ ipaka Ornani, ara Jebusi. 19 Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa. 20 Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ. 21 Bi Dafidi si ti de ọdọ Ornani, Ornani si wò, o si ri Dafidi, o si ti ibi ilẹ ipaka rẹ̀ jade, o si wolẹ, o dojubolẹ fun Dafidi. 22 Dafidi si wi fun Ornani pe, Fun mi ni ibi ipaka yi, ki emi ki o le tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa; iwọ o si fi fun mi ni iye owo rẹ̀ pipe; ki a le da ajakalẹ arun duro lọdọ awọn enia. 23 Ornani si wi fun Dafidi pe, Mu u fun ra rẹ, si jẹ ki oluwa mi ọba ki o ṣe eyiti o dara loju rẹ̀: wò o mo fi awọn malu pẹlu fun ẹbọ-ọrẹ-sisun, ati ohun èlo ipaka fun igi, ati ọka fun ọrẹ onjẹ; mo fi gbogbo rẹ̀ fun ọ. 24 Dafidi ọba si wi fun Ornani pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi a rà a ni iye owo rẹ̀ pipe nitõtọ, nitoriti emi kì o mu eyi ti iṣe tirẹ fun Oluwa, bẹ̃ni emi kì o ru ẹbọ-ọrẹ sisun laiṣe inawo. 25 Bẹ̃ni Dafidi fi ẹgbẹta ṣekeli wura nipa iwọn fun Ornani fun ibẹ na. 26 Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na. 27 Oluwa si paṣẹ fun angeli na; on si tun tẹ ida rẹ̀ bọ inu akọ rẹ̀. 28 Li akokò na nigbati Dafidi ri pe Oluwa ti da on li ohùn ni ibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi, o si rubọ nibẹ. 29 Nitori agọ Oluwa ti Mose pa li aginju, ati pẹpẹ ọrẹ sisun, mbẹ ni ibi giga ni Gibeoni li akokò na. 30 Ṣugbọn Dafidi kò le lọ siwaju rẹ̀ lati bere lọwọ Ọlọrun: nitoriti ẹ̀ru idà angeli Oluwa na ba a.

1 Kronika 22

1 NIGBANA ni Dafidi wipe, Eyi ni ile Oluwa Ọlọrun, eyi si ni pẹpẹ ọrẹ-sisun fun Israeli.

Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili

2 Dafidi si paṣẹ lati ko awọn alejo ti mbẹ ni ilẹ Israeli jọ; o si yan awọn agbẹkuta lati gbẹ okuta lati fi kọ́le Ọlọrun. 3 Dafidi si pese irin li ọ̀pọlọpọ fun iṣo fun ilẹkun ẹnu-ọ̀na, ati fun ìde; ati idẹ li ọ̀pọlọpọ li aini iwọn; 4 Igi kedari pẹlu li ainiye: nitori awọn ara Sidoni, ati awọn ti Tire mu ọ̀pọlọpọ igi kedari wá fun Dafidi. 5 Dafidi si wipe, Solomoni ọmọ mi, ọdọmọde ni, o si rọ̀, ile ti a o si kọ́ fun Oluwa, a o si ṣe e tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ: nitorina emi o pese silẹ fun u. Bẹ̃ni Dafidi si pese silẹ lọ̀pọlọpọ, ki o to kú. 6 Nigbana li o pe Solomoni ọmọ rẹ̀, o si fi aṣẹ fun u lati kọ́le kan fun Oluwa Ọlọrun Israeli. 7 Dafidi si wi fun Solomoni pe, Ọmọ mi, bi o ṣe ti emi ni, o ti wà li ọkàn mi lati kọ́le kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi: 8 Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi. 9 Kiyesi i, a o bi ọmọ kan fun ọ, ẹniti yio ṣe enia isimi; emi o si fun u ni isimi lọdọ gbogbo awọn ọta rẹ̀ yika kiri: nitori orukọ rẹ̀ yio ma jẹ Solomoni, emi o si fi alafia ati idakẹjẹ fun Israeli li ọjọ aiye rẹ̀. 10 On o kọ ile kan fun orukọ mi; on o si jẹ ọmọ mi; emi o si jẹ baba fun u; emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ mulẹ lori Israeli lailai. 11 Njẹ ọmọ mi, ki Oluwa ki o pẹlu rẹ; iwọ si ma pọ̀ si i, ki o si kọ́ ile Oluwa Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ nipa tirẹ. 12 Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́. 13 Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ. 14 Si kiyesi i, ninu ipọnju mi, emi ti pèse fun ile Oluwa na, ọkẹ marun talenti wura, ati ẹgbẹrun ẹgbẹrun talenti fadakà; ati ti idẹ, ati ti irin, laini ìwọn; nitori ọ̀pọlọpọ ni: ati ìti-igi ati okuta ni mo ti pèse; iwọ si le wá kún u. 15 Pẹlupẹlu awọn oniṣẹ mbẹ fun ọ lọpọlọpọ, awọn gbẹnagbẹna ati awọn oniṣọna okuta ati igi ati onirũru ọlọgbọ́n enia fun onirũru iṣẹ. 16 Niti wura, fadakà ati idẹ, ati irin, kò ni ìwọn. Nitorina dide ki o si ma ṣiṣẹ, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ. 17 Dafidi paṣẹ pẹlu fun gbogbo awọn ijoye Israeli lati ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọwọ pe: 18 Oluwa Ọlọrun nyin kò ha wà pẹlu nyin? on kò ha ti fi isimi fun nyin niha gbogbo? on sa ti fi awọn ti ngbe ilẹ na le mi li ọwọ; a si ṣẹgun ilẹ na niwaju Oluwa ati niwaju enia rẹ̀. 19 Njẹ nisisiyi ẹ fi aiya nyin ati ọkàn nyin si atiwá Oluwa Ọlọrun nyin; nitorina dide ki ẹ si kọ́ ibi mimọ́ Oluwa Ọlọrun, lati mu apoti ẹri ti majẹmu Oluwa wọ̀ inu rẹ̀, ati ohun èlo mimọ́ Ọlọrun, sinu ile na ti a o kọ́ fun orukọ Oluwa.

1 Kronika 23

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi

1 NIGBATI Dafidi gbó, ti o si kún fun ọjọ, o fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lori Israeli. 2 O si kó gbogbo awọn ijoye Israeli jọ, ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi. 3 A si ka awọn ọmọ Lefi lati ẹni ọgbọ̀n ọdun ati jù bẹ̃ lọ: iye wọn nipa ori wọn, ọkunrin kọkan sí jẹ ẹgbã mọkandilogun. 4 Ninu wọnyi, ẹgbã mejila ni lati ma bojuto iṣẹ ile Oluwa; ẹgbãta si nṣe olori ati onidajọ: 5 Ẹgbaji si jẹ adena: ẹgbaji si fi ohun-elo ti mo ṣe lati buyìn, yìn Oluwa. 6 Dafidi si pín wọn ni ẹgbẹgbẹ lãrin awọn ọmọ Lefi, eyini ni Gerṣoni, Kohati, ati Merari. 7 Ninu awọn ọmọ Gerṣoni ni Laadani, ati Ṣimei. 8 Awọn ọmọ Laadani: Jehieli ni olori, ati Setamu, ati Joeli, mẹta. 9 Awọn ọmọ Ṣimei; Ṣelomiti, ati Hasieli, ati Harani, mẹta. Awọn wọnyi li olori awọn baba Laadani. 10 Awọn ọmọ Ṣimei ni Jahati, Sina, ati Jeuṣi, ati Beriah. Awọn mẹrin wọnyi li ọmọ Ṣimei. 11 Jahati si li olori, ati Sisa ibikeji: ṣugbọn Jeuṣi ati Beriah kò li ọmọ pipọ; nitorina ni nwọn ṣe wà ni iṣiro kan, gẹgẹ bi ile baba wọn. 12 Awọn ọmọ Kohati; Amramu, Ishari, Hebroni ati Ussieli, mẹrin. 13 Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai. 14 Ṣugbọn niti Mose enia Ọlọrun, a kà awọn ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ ẹ̀ya Lefi. 15 Awọn ọmọ Mose ni, Gerṣomu ati Elieseri. 16 Ninu awọn ọmọ Gerṣomu, Sebueli li olori. 17 Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi. 18 Ninu awọn ọmọ Ishari; Ṣelomiti li olori. 19 Ninu awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ekini, Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, ati Jekamami ẹkẹrin. 20 Ninu awọn ọmọ Ussieli: Mika ekini, ati Jesiah ekeji. 21 Awọn ọmọ Merari; Mali ati Muṣi. Awọn ọmọ Mali; Eleasari ati Kiṣi. 22 Eleasari kú, kò si li ọmọkunrin bikòṣe ọmọbinrin: awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Kiṣi si fẹ wọn li aiya. 23 Awọn ọmọ Muṣi; Mali, ati Ederi, ati Jeremoti, mẹta. 24 Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ. 25 Nitori Dafidi wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli ti fi isimi fun awọn enia rẹ̀, on si ngbé Jerusalemu lailai: 26 Ati pẹlu awọn ọmọ Lefi: nwọn kì yio si tun rù ibugbe na mọ, ati gbogbo ohun elo rẹ̀ fun ìsin rẹ̀. 27 Nitori nipa ọ̀rọ ikẹhin Dafidi, ni kika iye awọn ọmọ Lefi lati ìwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ: 28 Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun; 29 Ati fun àkara ifihàn, ati fun iyẹfun kikuna fun ẹbọ ọrẹ, ati fun àkara alaiwu, ati fun eyi ti a yan ninu awo pẹtẹ, ati fun eyi ti a dín, ati fun gbogbo oniruru òṣuwọn ati ìwọn; 30 Ati lati duro li orowurọ lati dupẹ ati lati yin Oluwa, ati bẹ̃ gẹgẹ li aṣalẹ; 31 Ati lati ru gbogbo ẹbọ ọrẹ sisun fun Oluwa li ọjọjọ isimi, ati li oṣù titun ati li ọjọ wọnni ti a pa li aṣẹ, ni iye, li ẹsẹsẹ gẹgẹ bi aṣẹ ti a pa fun wọn nigbagbogbo niwaju Oluwa: 32 Ati ki nwọn ki o ma tọju ẹṣọ agọ ajọ enia, ati ẹṣọ ibi mimọ́, ati ẹṣọ awọn ọmọ Aaroni arakunrin wọn, ni ìsin ile Oluwa.

1 Kronika 24

Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáà

1 NJẸ bi a ti pín awọn ọmọ Aaroni ni wọnyi. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari. 2 Ṣugbọn Nadabu ati Abihu kú ṣaju baba wọn, nwọn kò si li ọmọ: nitorina ni Eleasari ati Itamari fi ṣiṣẹ alufa. 3 Dafidi si pin wọn, ati Sadoku ninu awọn ọmọ Eleasari, ati Ahimeleki ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi iṣẹ wọn ninu ìsin wọn. 4 A si ri awọn ọkunrin ti o nṣe olori ninu awọn ọmọ Eleasari jù ti inu awọn ọmọ Itamari lọ, bayi li a si pin wọn. Ninu awọn ọmọ Eleasari, ọkunrin mẹrindilogun li o nṣe olori ni ile baba wọn, ati mẹjọ ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi ile baba wọn. 5 Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari. 6 Ati Ṣemaiah ọmọ Nataneeli akọwe, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi kọ wọn niwaju ọba, ati awọn olori, ati Sadoku alufa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati niwaju olori awọn baba awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi: a mu ile baba kan fun Eleasari, a si mu ọkan fun Itamari. 7 Njẹ iṣẹkeké ekini jade fun Jehoiaribu, ekeji fun Jedaiah, 8 Ẹkẹta fun Harimu, ẹkẹrin fun Seorimu, 9 Ẹkarun fun Malkijah, ẹkẹfa fun Mijamini, 10 Ekeje fun Hakkosi, ẹkẹjọ fun Abijah, 11 Ẹkẹsan fun Jeṣua, ẹkẹwa fun Ṣekaniah, 12 Ẹkọkanla fun Eliaṣibu, ekejila fun Jakimu, 13 Ẹkẹtala fun Huppa, ẹkẹrinla fun Jeṣebeabu, 14 Ẹkẹdogun fun Bilga, ẹkẹrindilogun fun Immeri, 15 Ẹkẹtadilogun fun Heṣiri, ekejidilogun fun Afisesi, 16 Ẹkọkandilogun fun Petahiah, ogun fun Jehesekeli, 17 Ẹkọkanlelogun fun Jakini, ekejilelogun fun Gamuli, 18 Ẹkẹtalelogun fun Delaiah, ẹkẹrinlelogun fun Maasiah. 19 Wọnyi ni itò wọn ni ìsin wọn lati lọ sinu ile Oluwa, gẹgẹ bi iṣe wọn nipa ọwọ Aaroni baba wọn, bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti paṣẹ fun u.

Orúkọ Àwọn Ọmọ Lefi

20 Iyokù awọn ọmọ Lefi ni wọnyi: Ninu awọn ọmọ Amramu; Ṣubaeli: ninu awọn ọmọ Ṣubaeli; Jehediah. 21 Nipa ti Rehabiah; ninu awọn ọmọ Rehabiah, ekini Iṣṣiah. 22 Ninu awọn Ishari; Ṣelomoti; ninu awọn ọmọ Ṣelomoti; Jahati. 23 Awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ikini; Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, Jekamamu ẹkẹrin. 24 Awọn ọmọ Ussieli; Mika: awọn ọmọ Mika; Ṣamiri. 25 Arakunrin Mika ni Iṣṣiah; ninu awọn ọmọ Iṣṣiah; Sekariah. 26 Awọn ọmọ Merari ni Mali ati Muṣi: awọn ọmọ Jaasiah; Beno; 27 Awọn ọmọ Merari nipa Jaasiah; Beno ati Ṣohamu, ati Sakkuri, ati Ibri. 28 Lati ọdọ Mali ni Eleasari ti wá, ẹniti kò li ọmọkunrin. 29 Nipa ti Kiṣi: ọmọ Kiṣi ni Jerameeli. 30 Awọn ọmọ Muṣi pẹlu; Mali, ati Ederi, ati Jerimoti. Wọnyi li ọmọ awọn ọmọ Lefi nipa ile baba wọn. 31 Awọn wọnyi pẹlu ṣẹ keké gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Aaroni niwaju Dafidi ọba ati Sadoku, ati Ahimeleki, ati awọn olori awọn baba awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: olori awọn baba gẹgẹ bi aburo rẹ̀.

1 Kronika 25

Àwọn Akọrin Inú Tẹmpili

1 PẸLUPẸLU Dafidi ati awọn olori ogun yà ninu awọn ọmọkunrin Asafu, ati Hemani, ati Jedutuni, fun ìsin yi, awọn ẹniti o ma fi duru ati psalteri, ati kimbali kọrin: ati iye awọn oniṣẹ gẹgẹ bi ìsin wọn jẹ: 2 Ninu awọn ọmọ Asafu, Sakkuri, ati Josefu, ati Netaniah, ati Asarela, awọn ọmọ Asafu labẹ ọwọ Asafu, ti o kọrin gẹgẹ bi aṣẹ ọba. 3 Ti Jedutuni: awọn ọmọ Jedutuni; Gedaliah, ati Seri, ati Jeṣaiah, Haṣabiah, ati Mattitiah, ati Ṣimei, mẹfa, labẹ ọwọ baba wọn Jedutuni, ẹniti o fi duru kọrin, lati ma dupẹ fun ati lati ma yìn Oluwa. 4 Ti Hemani: awọn ọmọ Hemani; Bukkiah, Mattaniah, Ussieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, ati Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu: 5 Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Hemani, woli ọba ninu ọ̀rọ Ọlọrun, lati ma gbé iwo na soke. Ọlọrun si fun Hemani li ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta. 6 Gbogbo awọn wọnyi li o wà labẹ ọwọ baba wọn, fun orin ile Oluwa, pẹlu kimbali, psalteri ati duru, fun ìsin ile Ọlọrun: labẹ ọwọ ọba, ni Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà. 7 Bẹ̃ni iye wọn, pẹlu awọn arakunrin wọn ti a kọ́ li orin Oluwa, ani gbogbo awọn ti o moye, jasi ọrinlugba o le mẹjọ. 8 Nwọn si ṣẹ keké fun iṣẹ; gbogbo wọn bakanna bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, ti olukọ bi ti ẹniti a nkọ́. 9 Iṣẹkeké ekini si jade wá fun Asafu si Josefu: ekeji si Gedaliah, ẹniti on pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀, jẹ mejila: 10 Ẹkẹta si Sakkuri, awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 11 Ẹkẹrin si Isri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 12 Ẹkarun si Netaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 13 Ẹkẹfa si Bukkiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 14 Ekeje si Jeṣarela, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 15 Ẹkẹjọ si Jeṣaiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 16 Ẹkẹsan si Mattaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 17 Ẹkẹwa si Ṣimei, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 18 Ẹkọkanla si Asareeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 19 Ekejila si Haṣabiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 20 Ẹkẹtala si Ṣubaeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 21 Ẹkẹrinla si Mattitiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 22 Ẹkẹ̃dogun si Jeremoti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 23 Ẹkẹrindilogun si Hananiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 24 Ẹkẹtadilogun si Joṣbekaṣa awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 25 Ekejidilogun si Hanani, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 26 Ẹkọkandilogun si Malloti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 27 Ogun si Eliata, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 28 Ẹkọkanlelogun si Hotiri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 29 Ekejilelogun si Giddalti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 30 Ẹkẹtalelogun si Mahasioti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: 31 Ẹkẹrinlelogun si Romamti-eseri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila.

1 Kronika 26

Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili

1 NITI ipin awọn adena: niti awọn ọmọ Kosa ni Meṣelemiah ọmọ Kore, ninu awọn ọmọ Asafu. 2 Ati awọn ọmọ Meṣelemiah ni Sekariah akọbi, Jediaeli ekeji, Sebadiah ẹkẹta, Jatnieli ẹkẹrin, 3 Elamu ẹkarun, Johanani ẹkẹfa, Elioenai ekeje. 4 Awọn ọmọ Obed-Edomu si ni Ṣemaiah akọbi, Jehosabadi ekeji, Joa ẹkẹta, ati Sakari ẹkẹrin, ati Netaneeli ẹkarun, 5 Ammieli ẹkẹfa, Issakari ekeje, Peulltai ẹkẹjọ: Ọlọrun sa bukún u. 6 Ati fun Ṣemaiah ọmọ rẹ̀ li a bi awọn ọmọ ti nṣe olori ni ile baba wọn: nitori alagbara akọni enia ni nwọn. 7 Awọn ọmọ Ṣemaiah; Otni, ati Refaeli, ati Obedi, Elsabadi, arakunrin ẹniti iṣe alagbara enia, Elihu, ati Semakiah. 8 Gbogbo wọnyi ti inu awọn ọmọ Obed-Edomu, ni: awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn arakunrin wọn, akọni enia ati alagbara fun ìsin na, jẹ mejilelọgọta lati ọdọ Obed-Edomu; 9 Meṣelemiah si ni awọn ọmọ ati arakunrin, alagbara enia, mejidilogun. 10 Hosa pẹlu, ninu awọn ọmọ Merari, ni ọmọ; Simri olori (nitori bi on kì iti iṣe akọbi ṣugbọn baba rẹ̀ fi jẹ olori), 11 Hilkiah ekeji, Tebaliah ẹkẹta, Sekariah ẹkẹrin: gbogbo awọn ọmọ ati awọn arakunrin Hosa jẹ mẹtala. 12 Ninu awọn wọnyi ni ipin awọn adena, ani ninu awọn olori ọkunrin, ti nwọn ni iṣẹ gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn, lati ṣe iranṣẹ ni ile Oluwa. 13 Nwọn si ṣẹ keké, bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, gẹgẹ bi ile baba wọn, fun olukuluku ẹnu-ọ̀na. 14 Iṣẹ keké iha ila-õrun bọ̀ sọdọ Ṣelemiah. Nigbana ni nwọn ṣẹ keké fun Sekariah ọmọ rẹ̀, ọlọgbọ́n igbimọ; iṣẹ keké rẹ̀ si bọ si iha ariwa. 15 Sọdọ Obed-Edomu niha gusù; ati sọdọ awọn ọmọ rẹ̀ niha ile Asuppimu (yara iṣura). 16 Ti Suppimu ati Hosa niha iwọ-õrun li ẹnu-ọ̀na Ṣalleketi, nibi ọ̀na igòke lọ, iṣọ kọju si iṣọ. 17 Niha ìla-õrùn awọn ọmọ Lefi mẹfa (nṣọ), niha ariwa mẹrin li ojojumọ, niha gusù mẹrin li ojojumọ, ati ninu Asuppimu (ile iṣura) mejimeji. 18 Ni ibasa niha iwọ-õrùn, mẹrin li ọ̀na igòke-lọ ati meji ni ibasa. 19 Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.

Àwọn Iṣẹ́ Mìíràn ninu Tẹmpili

20 Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́. 21 Awọn ọmọ Laadani; awọn ọmọ Laadani ara Gerṣoni, awọn olori baba, ani ti Laadani ara Gerṣoni ni Jehieli. 22 Awọn ọmọ Jehieli; Setamu, ati Joeli arakunrin rẹ̀, ti o wà lori iṣura ile Oluwa. 23 Ninu ọmọ Amramu, ati ọmọ Ishari, ara Hebroni, ati ọmọ Ussieli: 24 Ati Ṣebueli ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, ni onitọju iṣura. 25 Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa Elieseri, Rehabiah ọmọ rẹ̀, ati Jesaiah ọmọ rẹ̀, ati Joramu, ọmọ rẹ̀, ati Sikri ọmọ rẹ̀, ati Ṣelomiti ọmọ rẹ̀. 26 Ṣelomiti yi ati awọn arakunrin rẹ̀ li o wà lori iṣura ohun iyà-si-mimọ́, ti Dafidi ọba ati awọn olori baba, awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn olori ogun ti yà-si-mimọ́. 27 Lati inu ikogun ti a kó li ogun, ni nwọn yà si mimọ́ lati ma fi ṣe itọju ile Oluwa. 28 Ati gbogbo eyiti Samueli, ariran, ati Saulu, ọmọ Kiṣi, ati Abneri ọmọ Neri, ati Joabu ọmọ Seruiah, yà si mimọ́; gbogbo ohun ti a ba ti yà si mimọ́, ohun na mbẹ li ọwọ Ṣelomiti, ati awọn arakunrin rẹ̀.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù

29 Ninu awọn ọmọ Ishari, Kenaniah ati awọn ọmọ rẹ̀ li o jẹ ijoye ati onidajọ fun iṣẹ ilu lori Israeli. 30 Ninu awọn ọmọ Hebroni, Hasabiah ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, ẽdẹgbẹsan li awọn alabojuto Israeli nihahin Jordani niha iwọ-õrun, fun gbogbo iṣẹ Oluwa, ati fun ìsin ọba. 31 Ninu awọn ọmọ Hebroni ni Jerijah olori, ani ninu awọn ọmọ Hebroni, gẹgẹ bi idile ati iran awọn baba rẹ̀. Li ogoji ọdun ijọba Dafidi, a wá wọn, a si ri ninu wọn, awọn alagbara akọni enia ni Jaseri ti Gileadi. 32 Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, jẹ ẹgbã o le ẽdẹgbẹrin: gbogbo wọn jẹ awọn olori baba ti Dafidi ọba fi ṣe olori lori awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, fun gbogbo ọ̀ran ti Ọlọrun ati ti ọba.

1 Kronika 27

Àwọn Ológun ati Ètò Òṣèlú

1 NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila. 2 Lori ẹgbẹ kini ti oṣù kini ni Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 3 Ninu awọn ọmọ Peresi on ni olori fun gbogbo awọn olori ogun ti oṣù ekini. 4 Ati lori ẹgbẹ ti oṣù keji ni Dodai ara Ahohi, ati ẹgbẹ tirẹ̀; Mikloti pẹlu nṣe balogun: ẹgbã mejila li o wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀ pẹlu. 5 Olori ogun kẹta fun oṣù kẹta ni Benaiah ọmọ Jehoiada alufa, olori kan: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 6 Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 7 Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 8 Olori ogun karun fun oṣù karun ni Ṣamhuti ara Israhi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 9 Olori ogun kẹfa fun oṣù kẹfa ni Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 10 Olori ogun keje fun oṣù keje ni Heleṣi ara Peloni, ninu awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 11 Olori ogun kẹjọ fun oṣù kẹjọ ni Sibbekai ara Huṣati ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 12 Olori ogun kẹsan fun oṣù kẹsan ni Abieseri ara Anatoti ti awọn ara Benjamini: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 13 Olori ogun kẹwa fun oṣù kẹwa ni Maharai ara Netofa, ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 14 Olori ogun kọkanla fun oṣù kọkanla ni Benaiah ara Peratoni, ti awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀. 15 Olori ogun kejila fun oṣù kejila ni Heldai ara Netofa, ti Otnieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

Ètò Àkóso Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

16 Ati lori awọn ẹ̀ya Israeli: ijoye lori awọn ọmọ Reubeni ni Elieseri ọmọ Sikri: lori awọn ọmọ Simeoni, Ṣefatiah ọmọ Maaka: 17 Lori awọn ọmọ Lefi, Haṣabiah ọmọ Kemueli: lori awọn ọmọ Aaroni, Sadoku: 18 Lori Juda, Elihu, ọkan ninu awọn arakunrin Dafidi: lori Issakari, Omri ọmọ Mikaeli: 19 Lori Sebuloni, Iṣmaiah ọmọ Obadiah: lori Naftali, Jerimoti ọmọ Asrieli: 20 Lori awọn ọmọ Efraimu, Hoṣea ọmọ Asasiah: lori àbọ ẹ̀ya Manasse, Joeli ọmọ Pedaiah. 21 Lori àbọ ẹ̀ya Manasse ni Gileadi, Iddo ọmọ Sekariah: lori Benjamini, Jaasieli ọmọ Abneri. 22 Lori Dani, Asareeli ọmọ Jerohamu Awọn wọnyi li olori awọn ẹ̀ya Israeli. 23 Ṣugbọn Dafidi kò ka iye awọn ti o wà lati ogun ọdun ati awọn ti kò to bẹ̃; nitori ti Oluwa ti wipe on o mu Israeli pọ̀ si i bi irawọ oju ọrun. 24 Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba. 25 Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà: 26 Ati lori awọn ti nro oko, lati ma ro ilẹ ni Esri ọmọ Kelubi wà: 27 Ati lori awọn ọgba-àjara ni Ṣimei ara Ramoti wà: lori eso ọgba-àjara fun iṣura ati ọti-waini ni Sabdi ọmọ Ṣifmi wà: 28 Ati lori igi-olifi, ati igi-sikamore ti mbẹ ni pẹ̀tẹlẹ ni Baal-hanani ara Gederi wà; ati lori iṣura ororo ni Joaṣi wà. 29 Ati lori awọn agbo malu ti njẹ̀ ni Ṣaroni ni Ṣitrai ara Ṣaroni wà: ati lori agbo malu ti o wà li afonifoji ni Ṣafati ọmọ Adlai wà: 30 Ati lori ibakasiẹ ni Obili ara Iṣmaeli wà: ati lori abo kẹtẹkẹtẹ ni Jehodaiah ara Meronoti wà: 31 Ati lori agbo agutan ni Jasisi ara Hageri wà. Gbogbo awọn wọnyi ni ijoye ohun ini ti iṣe ti Dafidi ọba.

Àwọn Olùdámọ̀ràn Dafidi Ọba

32 Jonatani ẹgbọn Dafidi pẹlu ni ìgbimọ ọlọgbọ́n enia ati akọwe: ati Jehueli ọmọ Hakmoni wà pẹlu awọn ọmọ ọba. 33 Ahitofeli si jẹ ìgbimọ ọba: ati Huṣai ara Arki ni ọrẹ ọba. 34 Ati lẹhin Ahitofeli ni Jehoiada ọmọ Benaiah, ati Abiatari: Joabu si ni arẹ-balogun ogun ọba.

1 Kronika 28

Ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀ fún kíkọ́ Tẹmpili

1 DAFIDI si kó gbogbo ijoye Israeli jọ, awọn ijoye ẹ̀ya, ati awọn ijoye awọn ẹgbẹ ti nṣe iranṣẹ fun ọba, ati awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati awọn ijoye lori ọrọrun, ati awọn ijoye lori gbogbo ọrọ̀ ati ini ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu awọn balogun, ati pẹlu awọn alagbara enia, ati gbogbo akọni enia si Jerusalemu. 2 Nigbana ni Dafidi ọba dide duro li ẹsẹ rẹ̀, o si wipe, Ẹ gbọ́ ti emi, ẹnyin arakunrin mi ati enia mi: emi fẹ li ọkàn mi lati kọ́ ile isimi kan fun apoti ẹri majẹmu Oluwa, ati fun itisẹ Ọlọrun wa, mo si ti mura tan fun kikọ́le na: 3 Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun mi pe, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitori ologun ni iwọ, o si ti ta ẹ̀jẹ silẹ. 4 Oluwa Ọlọrun Israeli si yàn mi lati inu gbogbo ile baba mi lati jẹ ọba lori Israeli lailai: nitori ti o ti yàn Juda li olori; ati ninu ile Juda, ile baba mi: ati larin awọn ọmọ baba mi o fẹ mi lati jẹ ọba gbogbo Israeli. 5 Ati ninu gbogbo ọmọ mi ọkunrin (nitori ti Oluwa ti fun mi li ọmọkunrin pupọ), o ti yàn Solomoni ọmọ mi lati joko lori itẹ ijọba Oluwa lori Israeli. 6 On si wi fun mi pe, Solomoni ọmọ rẹ, on yio kọ́ ile mi ati agbala mi: nitori emi ti yàn a li ọmọ mi, emi o si jẹ baba fun u. 7 Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi. 8 Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai. 9 Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai. 10 Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e. 11 Nigbana ni Dafidi fi apẹrẹ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ ti iloro, ati ti ile rẹ̀, ati ti ibi iṣura rẹ̀, ati ti iyara-òke rẹ̀, ati ti gbangan inu rẹ̀ ati ti ibi ibujoko ãnu, 12 Ati apẹrẹ gbogbo eyi ti o ni ni inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀ niti agbala ile Oluwa, ati ti gbogbo iyara yikakiri, niti ibi iṣura ile Ọlọrun, ati niti ibi iṣura ohun ti a yà-si-mimọ́: 13 Niti ipin awọn alufa pẹlu ati ti awọn ọmọ Lefi, ati niti gbogbo iṣẹ ìsin ile Oluwa, ati niti gbogbo ohun èlo ìsin ni ile Oluwa. 14 Niti wura nipa ìwọn ti wura, niti gbogbo ohun èlo oniruru ìsin; niti gbogbo ohun èlo fadakà nipa ìwọn, niti gbogbo ohun èlo fun oniruru ìsin: 15 Ati ìwọn ọpa fitila wura, ati fitila wura wọn, nipa ìwọn fun olukuluku ọpa fitila ati ti fitila rẹ̀: ati niti ọpa fitila fadakà nipa ìwọn, ti olukuluku ọpa fitila ati ti fitila rẹ̀, gẹgẹ bi ìlo olukuluku ọpa fitila. 16 Ati wura nipa ìwọn fun tabili àkara ifihan, fun olukuluku tabili; ati fadakà fun tabili fadakà: 17 Ati wura didara fun pàlaka mimu ẹran, ati ọpọn, ati ago: ati fun awo-koto wura nipa ìwọn fun olukuluku awo-koto; ati nipa ìwọn fun olukuluku awo-koto fadakà: 18 Ati fun pẹpẹ turari, wura daradara nipa ìwọn; ati apẹrẹ iduro awọn kerubu ti wura, ti nwọn nà iyẹ wọn, ti nwọn si bo apoti ẹri majẹmu Oluwa mọlẹ 19 Gbogbo eyi wà ninu iwe lati ọwọ Oluwa ẹniti o kọ́ mi niti gbogbo iṣẹ apẹrẹ wọnyi. 20 Dafidi si sọ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, murale ki o si gboyà, ki o si ṣiṣẹ: má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe dãmu: nitori Oluwa Ọlọrun, ani Ọlọrun mi wà pẹlu rẹ; on kì yio yẹ̀ ọ, bẹ̃ni kì yio kọ̀ ọ silẹ titi iwọ o fi pari gbogbo iṣẹ fun ìsin ile Oluwa. 21 Si kiyesi i, ipin awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, wà pẹlu rẹ fun oniruru ìsin ile Ọlọrun: iwọ ni pẹlu rẹ oniruru enia, ọlọkàn fifẹ, ẹniti o ni oye gbogbo iṣẹ fun oniruru iṣẹ: pẹlupẹlu awọn ijoye ati gbogbo awọn enia wà pẹlu rẹ fun gbogbo ọ̀ran rẹ.

1 Kronika 29

Àwọn Ẹ̀bùn láti fi Kọ́ Tẹmpili

1 DAFIDI ọba si wi fun gbogbo ijọ enia pe, Solomoni ọmọ mi, on nikan ti Ọlọrun ti yàn, jẹ ọmọde o si rọ̀, iṣẹ na si tobi: nitori ti ãfin na kì iṣe fun enia, ṣugbọn fun Ọlọrun Oluwa. 2 Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tẹ̀ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọ̀pọlọpọ. 3 Pẹlupẹlu, nitori ni didùn inu mi si ile Ọlọrun mi, mo fi ohun ini mi, eyinì ni wura ati fadakà, fun ile Ọlọrun mi, jù gbogbo eyi ti mo ti pèse silẹ fun ile mimọ́ na, 4 Ẹgbẹ̃dogun talenti wura, ti wura Ofiri, ati ẹ̃dẹgbarin talenti fadakà didara, lati fi bo ogiri ile na: 5 Wura fun ohun èlo wura, ati fadakà fun ohun èlo fadakà, ati fun oniruru iṣẹ nipa ọwọ awọn ọlọnà. Tani si nfẹ loni lati yà ara rẹ̀ si mimọ fun Oluwa? 6 Nigbana ni awọn olori awọn baba ati awọn ijoye ẹ̀ya Israeli, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun, pẹlu awọn ijoye iṣẹ ọba fi tinutinu ṣe iranlọwọ, 7 Nwọn si fi fun iṣẹ ile Ọlọrun, ti wura ẹgbẹ̃dọgbọ̀n talenti ati ẹgbãrun dramu, ati ti fadakà ẹgbãrun talenti, ati ti bàba ẹgbãsan talenti, ati ọkẹ marun talenti irin. 8 Ati awọn ti a ri okuta iyebiye lọdọ wọn fi i sinu iṣura ile Oluwa, nipa ọwọ Jehieli ara Gerṣoni. 9 Awọn enia si yọ̀, nitori nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ nitori pẹlu ọkàn pipe ni nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun Oluwa: pẹlupẹlu Dafidi ọba si yọ̀ gidigidi.

Dafidi fi Ìyìn fún Ọlọrun

10 Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai! 11 Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: nitori ohun gbogbo li ọrun ati li aiye tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a si gbé ọ leke li ori fun ohun gbogbo. 12 Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọdọ rẹ ni ti iwá, iwọ si jọba lori ohun gbogbo; li ọwọ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati li ọwọ rẹ ni sisọ ni di nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo. 13 Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yìn orukọ ogo rẹ. 14 Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ. 15 Nitori alejo ni awa niwaju rẹ, ati atipo bi gbogbo awọn baba wa: ọjọ wa li aiye dabi ojiji, kò si si ireti. 16 Oluwa Ọlọrun wa, gbogbo ohun ọ̀pọlọpọ yi ti awa ti pèse silẹ lati kọ ile fun ọ fun orukọ rẹ mimọ́, lati ọwọ rẹ wá ni, ati gbogbo rẹ̀ jẹ tirẹ. 17 Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ. 18 Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Israeli, awọn baba wa, pa eyi mọ́ lailai sinu ete ironu ọkàn awọn enia rẹ, si fi idi ọkàn wọn mulẹ si ọdọ rẹ: 19 Si fi ọkàn pipe fun Solomoni ọmọ mi lati pa ofin rẹ, ẹri rẹ, ati ilana rẹ mọ́, ati lati ṣe ohun gbogbo, ati lati kọ́ ãfin, fun eyi ti mo ti pèse silẹ. 20 Dafidi si sọ fun gbogbo ijọ enia pe, Nisisiyi ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin. Gbogbo enia si fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si tẹ ori wọn ba, nwọn wolẹ fun Oluwa ati ọba. 21 Nwọn si ru ẹbọ si Oluwa, nwọn si ru ẹbọ sisun si Oluwa, li ọjọ keji lẹhin ọjọ na, ẹgbẹrun akọmalu, ẹgbẹrun àgbo, ẹgbẹrun ọdọ-agutan, pẹlu ọrẹ mimu wọn, ati ẹbọ miran li ọ̀pọlọpọ fun gbogbo Israeli: 22 Nwọn si jẹ nwọn si mu niwaju Oluwa li ọjọ na pẹlu ayọ̀ nla. Nwọn si tun fi Solomoni ọmọ Dafidi jọba li ẹ̃keji, a si fi ororo yàn a li ọba, ati Sadoku li alufa. 23 Bẹ̃ni Solomoni joko lori itẹ Oluwa bi ọba ni ipò Dafidi baba rẹ̀, o si pọ̀ si i; gbogbo Israeli si gba tirẹ̀ gbọ́. 24 Ati gbogbo awọn ijoye, ati awọn alagbara, ati pẹlu gbogbo awọn ọmọ Dafidi ọba tẹri wọn ba fun Solomoni ọba. 25 Oluwa si gbé Solomoni ga gidigidi li oju gbogbo Israeli, o si fi ọlá nla ọba fun u bi iru eyi ti kò wà fun ọba kan ṣaju rẹ̀ lori Israeli.

Àkójọpọ̀ Ìjọba Dafidi

26 Dafidi ọmọ Jesse si jọba lori gbogbo Israeli. 27 Akokò ti o si fi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun; ọdun meje li o jọba ni Hebroni, ati mẹtalelọgbọn li o jọba ni Jerusalemu. 28 On si darugbó, o kú rere, o kún fun ọjọ, ọrọ̀ ati ọlá; Solomoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. 29 Njẹ iṣe Dafidi ọba, ibẹ̀rẹ ati ikẹhin, kiyesi i, a kọ ọ sinu iwe Samueli ariran, ati sinu iwe itan Natani woli, ati sinu iwe itan Gadi ariran. 30 Pẹlu gbogbo jijọba ati ipá rẹ̀, ati ìgba ti o kọja lori rẹ̀, ati lori Israeli, ati lori gbogbo ijọba ilẹ wọnni.

2 Kronika 1

Solomoni Ọba Gbadura fún Ọgbọ́n

1 A si mu Solomoni, ọmọ Dafidi, lagbara lori ijọba rẹ̀, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ si wà pẹlu rẹ̀, o si gbé e ga gidigidi. 2 Solomoni si sọ fun gbogbo Israeli, fun awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati fun awọn onidajọ, ati fun gbogbo awọn bãlẹ ni gbogbo Israeli, awọn olori awọn baba. 3 Solomoni ati gbogbo awọn ijọ enia pẹlu rẹ̀, lọ si ibi giga ti o wà ni Gibeoni; nitori nibẹ ni agọ ajọ enia Ọlọrun gbe wà, ti Mose, iranṣẹ Oluwa ti pa ni aginju. 4 Apoti-ẹri Ọlọrun ni Dafidi ti gbé lati Kirjat-jearimu wá si ibi ti Dafidi ti pese silẹ fun u, nitoriti o ti pa agọ kan silẹ fun u ni Jerusalemu. 5 Ṣugbọn pẹpẹ idẹ ti Besaleeli, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe, wà nibẹ niwaju agọ Oluwa: Solomoni ati ijọ enia si wá a ri. 6 Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀. 7 Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ. 8 Solomoni si wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti fi ãnu nla hàn baba mi, o si ti mu mi jọba ni ipò rẹ̀. 9 Nisisiyi Oluwa Ọlọrun, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ fun Dafidi baba mi ṣẹ: nitoriti iwọ ti fi mi jọba lori awọn enia ti o pọ̀ bi erupẹ ilẹ. 10 Fun mi li ọgbọ́n ati ìmọ nisisiyi, ki emi le ma wọ ile, ki nsi ma jade niwaju enia yi: nitoripe, tani le ṣe idajọ enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi. 11 Ọlọrun si wi fun Solomoni pe, Nitoriti eyi wà li aiya rẹ, ti iwọ kò si bère ọrọ̀, ọlà, tabi ọlá, tabi ẹmi awọn ọta rẹ, bẹ̃ni o kò tilẹ bère ẹmi gigun, ṣugbọn o bère ọgbọ́n fun ara rẹ, ki o le ma ṣe idajọ enia mi, lori ẹniti mo fi ọ jọba: 12 Nitorina a fi ọgbọ́n on ìmọ fun ọ, Emi o si fun ọ ni ọrọ̀, ọlá, tabi ọlà, iru eyiti ọba kan ninu awọn ti nwọn wà ṣaju rẹ kò ni ri, bẹ̃ni lẹhin rẹ kì yio si ẹniti yio ni iru rẹ̀.

Agbára Solomoni ati Ọrọ̀ Rẹ̀

13 Solomoni si pada lati ibi giga ti o wà ni Gibeoni wá si Jerusalemu, lati iwaju agọ ajọ awọn enia, o si jọba lori Israeli. 14 Solomoni ko kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin jọ: o si ni ẹgbãje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹṣin, ti o fi sinu ilu kẹkẹ́ ati pẹlu ọba ni Jerusalemu. 15 Ọba si ṣe ki fadakà ati wura ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti o wà ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ. 16 A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti, ati okùn-ọ̀gbọ: awọn oniṣowo ọba ngbà okùn-ọ̀gbọ na ni iye kan. 17 Nwọn si gòke, nwọn si mu kẹkẹ́ kan lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu ẹṣin jade fun gbogbo awọn ọba ara Hitti, ati fun awọn ọba Siria nipa wọn.

2 Kronika 2

Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili

1 SOLOMONI si pinnu rẹ̀ lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, ati ile kan fun ijọba rẹ̀. 2 Solomoni si yàn ẹgbã marundilogoji ọkunrin lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ké igi li ori òke, ati egbejidilogun lati bojuto wọn. 3 Solomoni si ranṣẹ si Huramu, ọba Tire, wipe, Gẹgẹ bi iwọ ti ba Dafidi, baba mi lò, ti iwọ fi igi kedari ṣọwọ si i lati kọ́ ile kan fun u lati ma gbe inu rẹ̀, bẹni ki o ba mi lò. 4 Kiyesi i, emi nkọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun mi, lati yà a si mimọ́ fun u, ati lati sun turari niwaju rẹ̀, ati fun àkara-ifihan igbakugba, ati fun ẹbọsisun li ọwurọ ati li alẹ, li ọjọjọ isimi ati li oṣoṣù titun, ati li apejọ Oluwa Ọlọrun wa; eyi ni aṣẹ fun Israeli titi lai. 5 Ile ti emi nkọ́ yio si tobi; nitori titobi ni Ọlọrun wa jù gbogbo awọn ọlọrun lọ. 6 Ṣugbọn tani to lati kọ́ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọ́le fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rẹ̀? 7 Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ. 8 Fi ìti-igi kedari, ati firi, ati algumu ranṣẹ si mi pẹlu, lati Lebanoni wá: emi sa mọ̀ pe awọn iranṣẹ rẹ le gbọ́ngbọn ati ké igi ni Lebanoni; si kiyesi i, awọn ọmọ-ọdọ mi yio wà pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ: 9 Ani lati pèse ìti-igi lọpọlọpọ silẹ fun mi: nitori ile na ti emi mura lati kọ́ tobi, o si ya ni lẹnu. 10 Si wò o, emi o fi fun ilo awọn akégi, ti nké ìti-igi, lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ẹgbãwa òṣuwọn alikama fun onjẹ, ati ẹgbãwa òṣuwọn barli ati ẹgbãwa bati ọti-waini, ati ẹgbãwa bati ororo. 11 Nigbana ni Huramu, ọba Tire, kọwe dahùn o si ranṣẹ si Solomoni pe, Nitori ti Oluwa fẹran awọn enia rẹ̀ li o ṣe fi ọ jọba lori wọn. 12 Huramu si wipe, Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o da ọrun on aiye, ẹniti o fun Dafidi ọba ni ọlọgbọ́n ọmọ, ti o mọ̀ ọgbọ́n ati oye, ti o le kọ́ ile fun Oluwa, ati ile fun ijọba rẹ̀. 13 Njẹ nisisiyi emi rán ọkunrin ọlọgbọ́n kan, ti o mọ̀ oye, ani Huramu-Abi, 14 Ọmọ obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin Dani: baba rẹ̀ si ṣe ọkunrin ara Tire ti o gbọ́ngbọn ati ṣiṣẹ ni wura, ati ni fadakà, ni idẹ, ni irin, ni okuta, ati ni ìti-igi, ni èse-aluko, ni alaró, ati ni ọ̀gbọ daradara, ati òdodó, lati gbẹ́ oniruru ohun gbigbẹ́ pẹlu, ati lati ṣe awari ìmọ ẹrọ gbogbo ti a o fi fun u ṣe, pẹlu awọn ọlọgbọ́n rẹ, ati pẹlu awọn ọlọgbọ́n oluwa mi Dafidi, baba rẹ. 15 Njẹ nitorina alikama ati ọkà barli, ororo, ati ọti-waini na ti oluwa mi ti sọ, jẹ ki o fi ranṣẹ si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. 16 Awa o si ké igi lati Lebanoni wá, iyekiye ti iwọ o fẹ; awa o si mu wọn fun ọ wá ni fifó li okun si Joppa; iwọ o si rù wọn gòke lọ si Jerusalemu.

Kíkọ́ Tẹmpili Bẹ̀rẹ̀

17 Solomoni si kaye gbogbo awọn ajeji ọkunrin ti o wà ni ilẹ Israeli, gẹgẹ bi kikà ti Dafidi, baba rẹ̀ ti kà wọn; a si ri pe, nwọn jẹ ọkẹ-mẹjọ o di-egbejilelọgbọ̀n. 18 O si yàn ẹgbã marundilogoji ninu wọn lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ṣe aké-okuta li ori òke, ati egbejidilogun alabojuto lati kó awọn enia ṣiṣẹ.

2 Kronika 3

1 SOLOMONI si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu li òke Moriah nibiti Ọlọrun farahàn Dafidi baba rẹ̀, ti Dafidi ti pèse, nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi. 2 On si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile ni ọjọ keji oṣù keji, li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. 3 Eyi si ni ìwọn ti Solomoni fi lelẹ fun kikọ́ ile Ọlọrun. Gigùn rẹ̀ ni igbọnwọ gẹgẹ bi ìwọn igbãni li ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ. 4 Ati iloro ti mbẹ niwaju ile na, gigùn rẹ̀ ri gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgọfa; o si fi kiki wura bò o ninu. 5 O si fi igi-firi bò ile ti o tobi, o si fi wura daradara bò o, o si gbẹ́ àworan igi-ọpẹ ati ẹ̀wọn si i. 6 O si fi okuta iyebiye ṣe ile na li ọṣọ́ fun ẹwà: wura na si jasi wura Parfaimu. 7 O si fi wura bò ile na pẹlu, ati ìti, opó, ati ogiri rẹ̀ wọnni, ati ilẹkun rẹ̀ mejeji; o si gbẹ́ àworan awọn kerubu si ara ogiri na. 8 O si ṣe ile mimọ́-jùlọ na, gigùn eyiti o wà gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ: ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ: o si fi wura daradara bò o, ti o to ẹgbẹta talenti. 9 Oṣuwọn iṣó si jasi ãdọta ṣekeli wura. On si fi wura bò iyara òke wọnni. 10 Ati ninu ile mimọ́-jùlọ na, o ṣe kerubu meji ti iṣẹ ọnà finfin, o si fi wura bò wọn. 11 Iyẹ awọn kerubu na si jẹ ogún igbọnwọ ni gigùn: iyẹ kan jẹ igbọnwọ marun, ti o kan ogiri ile na, iyẹ keji si jẹ igbọnwọ marun, ti o kan iyẹ kerubu keji. 12 Ati iyẹ kerubu keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan ogiri ile na: ati iyẹ keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan iyẹ kerubu keji. 13 Iyẹ kerubu wọnyi nà jade ni ogún igbọnwọ: nwọn si duro li ẹsẹ wọn, oju wọn si wà kọju si ile. 14 O si ṣe iboju alaro, ati elése aluko ati òdodó, ati ọ̀gbọ daradara, o si ṣiṣẹ awọn kerubu lara wọn.

Àwọn Òpó Idẹ Meji

15 O si ṣe ọwọ̀n meji igbọnwọ marundilogoji ni giga niwaju ile na, ati ipari ti mbẹ lori ọkọkan wọn si jẹ igbọnwọ marun. 16 O si ṣe ẹ̀wọn ninu ibi-idahùn na, o si fi wọn si ori awọn ọwọ̀n na: o si ṣe awọn pomegranate ọgọrun, o si fi wọn si ara ẹ̀wọn na. 17 O si gbé awọn ọwọ̀n na ro niwaju ile Ọlọrun, ọkan li apa ọtún, ati ekeji li apa òsi, o si pe orukọ eyi ti mbẹ li apa ọtún ni Jakini, ati orukọ eyi ti mbẹ li apa òsi ni Boasi.

2 Kronika 4

Àwọn Ohun Èlò Inú Tẹmpili

1 O si ṣe pẹpẹ idẹ kan, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ si ni ibu rẹ̀, ati igbọnwọ mẹwa ni giga rẹ̀. 2 O si ṣe agbada didà nla, igbọnwọ mẹwa lati eti kan de eti ekeji, o ṣe birikiti, igbọnwọ marun si ni giga rẹ̀; okùn ọgbọ̀n igbọ̀nwọ li o si yi i kakiri: 3 Aworan malu si wà labẹ rẹ̀ yi i kakiri, nwọn si lọ yi agbada nla na kakiri: igbọnwọ mẹwa yi i ka, ọwọ́ meji malu li a dà ni didà wọn kan. 4 O duro lori malu mejila wọnni, mẹta nwò iha ariwa, ati mẹta nwò iwọ-õrun, ati mẹta nwò gusu ati mẹta nwò iha ilà-orun: a si gbé agbada na ka ori wọn, gbogbo iha ẹhin wọn si wà ninu. 5 O si nipọn to ibu atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà, o si da ẹgbẹdogun ìwọn bati duro. 6 O ṣe agbada mẹwa pẹlu, o si fi marun si apa ọtún, ati marun si apa òsi, lati wẹ̀ ninu wọn: iru nkan ti nwọn fi nrubọ sisun ni nwọn nwẹ̀ ninu wọn; ṣugbọn agbada na ni fun awọn alufa lati ma wẹ̀. 7 O si ṣe ọpa-fitila wura mẹwa gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, o si fi wọn sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi. 8 O si ṣe tabili mẹwa, o si fi sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi. O si ṣe ọgọrun ọpọ́n wura. 9 O ṣe agbala awọn alufa pẹlu, ati agbala nla, ati ilẹkun fun agbala nla na, o si fi idẹ bo awẹ meji ilẹkun wọn. 10 O si fi agbada na si apa ọtún igun ile ila-õrun, si idojukọ gusu. 11 Huramu si ṣe ikoko, ati ọkọ́ ati ọpọ́n. Huramu si pari iṣẹ na ti o ni iṣe fun Solomoni ọba ni ile Ọlọrun; 12 Ọwọ̀n meji ati ọta, ati ọpọ́n ti o wà li ori ọwọ̀n mejeji na, ati iṣẹ ẹ̀wọn meji lati bo ọta meji ti ọpọ́n na, ti o wà li ori awọn ọwọ̀n na; 13 Ati irinwo pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn meji na, ẹsẹ meji pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn kan, lati bo ọta meji na ti ọpọ́n ti o wà lori awọn ọwọ̀n na. 14 O si ṣe ijoko, o si ṣe agbada li ori awọn ijoko na. 15 Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ rẹ̀. 16 Ati ikoko ati ọkọ́, ati kọkọrọ-ẹran, ati gbogbo ohun-elo ni Huramu-Abi fi idẹ didan ṣe fun Solomoni ọba, fun ile Oluwa. 17 Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ li agbedemeji Sukkoti ati Seredata. 18 Bayi ni Solomoni ṣe gbogbo ohun-elo wọnyi li ọ̀pọlọpọ: nitori ti a kò le mọ̀ ìwọn idẹ na. 19 Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Ọlọrun, pẹpẹ wura pẹlu, ati awọn tabili lori eyi ti akara ifihan wà; 20 Ọpa-fitila pẹlu ati fitila wọn, ki nwọn ki o ma jo gẹgẹ bi aṣẹ niwaju ibi-mimọ́-jùlọ, jẹ wura daradara. 21 Ati itanna, ati fitila ati ẹ̀mu li o fi wura ṣe; gbogbo eyi ni wura daradara; 22 Ati alumagaji fitila, ati awo-koto, ati ṣibi ati awo-koto turari, wura daradara ni: ati ọ̀na iwọle, awẹ ilẹkun rẹ̀ ti inu lọhun fun ibi-mimọ́-jùlọ, ati awọn ilẹkun fun ile na, ani tempili, wura ni.

2 Kronika 5

1 BAYI ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ṣe fun ile Oluwa pari: Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá sinu rẹ̀; ati fadakà, ati wura, ati gbogbo ohun-elo, li o fi sinu iṣura ile Ọlọrun.

Gbígbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sinu Tẹmpili

2 Nigbana ni Solomoni pe awọn àgbagba Israeli jọ, ati gbogbo olori awọn baba awọn ọmọ Israeli si Jerusalemu, lati mu apoti-ẹri majẹmu Oluwa gòke lati ilu Dafidi wá, ti iṣe Sioni. 3 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pejọ sọdọ ọba li ajọ, eyi ni oṣù keji. 4 Gbogbo awọn àgbagba Israeli si wá; awọn ọmọ Lefi si gbé apoti-ẹri na. 5 Nwọn si gbé apoti-ẹri na gòke, ati agọ ajọ, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ, wọnyi ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu gòke wá. 6 Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀, wà niwaju apoti-ẹrí na, nwọn si fi agutan ati malu rubọ, ti a kò le kà, bẹ̃ni a kò le mọ̀ iye wọn fun ọ̀pọlọpọ. 7 Awọn alufa si gbé apoti-ẹri ti majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀, si ibi-idahùn ile na, sinu ibi-mimọ́-jùlọ, labẹ iyẹ awọn kerubu: 8 Bẹ̃ni awọn kerubu nà iyẹ wọn bò ibi apoti-ẹri na, awọn kerubu si bò apoti-ẹri na, ati awọn ọpa rẹ̀ lati òke wá. 9 Ọpa rẹ̀ wọnni si gùn tobẹ̃, ti a fi ri ori awọn ọpa na lati ibi apoti-ẹri na niwaju ibi mimọ́-jùlọ na, ṣugbọn a kò ri wọn li ode. Nibẹ li o si wà titi di oni yi. 10 Kò si ohun kan ninu apoti-ẹri na bikòṣe walã meji ti Mose fi sinu rẹ̀ ni Horebu, nigbati Oluwa fi ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti Egipti jade wá.

Ògo OLUWA

11 O si ṣe, nigbati awọn alufa ti ibi mimọ́ jade wá; (nitori gbogbo awọn alufa ti a ri li a yà si mimọ́, nwọn kò si kiyesi ipa wọn nigbana: 12 Awon ọmọ Lefi pẹlu ti iṣe akọrin, gbogbo wọn ti Asafu, ti Hemani, ti Jedutuni, pẹlu awọn ọmọ wọn ati awọn arakunrin wọn, nwọn wọ ọ̀gbọ funfun, nwọn ni kimbali, ati ohun-elo orin, ati duru, nwọn si duro ni igun ila-õrun pẹpẹ na, ati pẹlu wọn, ìwọn ọgọfa alufa ti nwọn nfún ipè:) 13 O si ṣe bi ẹnipe ẹnikan, nigbati a gbọ́ ohùn awọn afunpè ati awọn akọrin, bi ohùn kan lati ma yìn, ati lati ma dupẹ fun Oluwa; nigbati nwọn si gbé ohùn wọn soke pẹlu ipè ati kimbali, ati ohun-elo orin, lati ma yìn Oluwa pe, O ṣeun; ãnu rẹ̀ si duro lailai: nigbana ni ile na kún fun awọsanmọ, ani ile Oluwa; 14 Tobẹ̃ ti awọn alufa kò le duro lati ṣiṣẹ ìsin nitori awọsanmọ na: nitori ogo Oluwa kún ile Ọlọrun.

2 Kronika 6

Ọ̀rọ̀ tí Solomoni Bá Àwọn Eniyan Sọ

1 NIGBANA ni Solomoni wipe, Oluwa ti wipe, on o ma gbe inu òkunkun biribiri. 2 Ṣugbọn emi ti kọ́ ile ibugbe kan fun ọ, ati ibi kan fun ọ lati ma gbe titi lai. 3 Ọba si yi oju Rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli; gbogbo ijọ awọn enia Israeli si dide duro. 4 O si wipe, Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ọwọ rẹ̀ mu eyi ti o ti fi ẹnu rẹ̀ sọ fun Dafidi baba mi ṣẹ, wipe, 5 Lati ọjọ ti emi ti mu awọn enia mi jade kuro ni ilẹ Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli lati kọ́ ile, ki orukọ mi ki o wà nibẹ; bẹ̃ni emi kò yàn ọkunrin kan lati ṣe olori Israeli awọn enia mi: 6 Ṣugbọn emi ti yàn Jerusalemu, ki orukọ mi ki o le wà nibẹ; mo si ti yàn Dafidi lati wà lori Israeli, enia mi. 7 O si ti wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli: 8 Oluwa si sọ fun Dafidi baba mi pe, nitoriti o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile fun orukọ mi, iwọ ṣeun li eyiti o wà li ọkàn rẹ. 9 Sibẹ iwọ kò gbọdọ kọ́ ile na; ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio jade ti inu rẹ wá ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. 10 Oluwa si ti mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ; emi si dide ni ipò Dafidi baba mi, a si gbé mi ka itẹ́ Israeli bi Oluwa ti ṣe ileri, emi si ti kọ́ ile na fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli. 11 Ati ninu rẹ̀ ni mo fi apoti-ẹri na si, ninu eyiti majẹmu Oluwa wà, ti o ba awọn ọmọ Israeli dá.

Adura Solomoni

12 On si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ ọwọ rẹ̀ mejeji. 13 Nitori Solomoni ṣe aga idẹ kan, igbọnwọ marun ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni gbigboro, ati igbọnwọ mẹta ni giga, o si gbé e si ãrin agbala na; lori rẹ̀ li o duro, o si kunlẹ lori ẽkun rẹ̀ niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji soke ọrun, 14 O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ li ọrun tabi li aiye: ti npa majẹmu mọ́, ati ãnu fun awọn iranṣẹ rẹ, ti nfi tọkàntọkan wọn rìn niwaju rẹ. 15 Iwọ ti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi baba mi, pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́; ti iwọ si ti fi ẹnu rẹ sọ, ti iwọ si ti fi ọwọ rẹ mu u ṣẹ, bi o ti ri loni yi. 16 Njẹ nisisiyi, Oluwa, Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́, wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ́ Israeli: kiki bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati ma rìn ninu ofin mi, bi iwọ ti rìn niwaju mi. 17 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ, ti iwọ ti sọ fun Dafidi, iranṣẹ rẹ, 18 Ni otitọ ni Ọlọrun yio ha ma ba enia gbe li aiye? Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ́! 19 Sibẹ, iwọ ṣe afiyesi adura iranṣẹ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati adura ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ: 20 Ki oju rẹ ki o le ṣí si ile yi lọsan ati loru, ani si ibi ti iwọ ti wipe, iwọ o fi orukọ rẹ sibẹ; lati tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ ngbà si ibi yi. 21 Nitorina gbọ́ ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati ti Israeli enia rẹ ti nwọn o ma gbà si ibi yi: iwọ gbọ́ lati ibugbe rẹ wá, ani lati ọrun wá, nigbati iwọ ba gbọ́, ki o si dariji. 22 Bi ọkunrin kan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, ti ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi; 23 Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni sisan a fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ pada sori on tikararẹ̀; ati ni didare fun olododo, lati fifun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀. 24 Bi a ba si fọ́ awọn enia rẹ Israeli bajẹ niwaju ọta, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ti nwọn ba si pada ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ niwaju rẹ ni ile yi; 25 Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun wọn ati fun awọn baba wọn. 26 Nigbati a ba se ọrun mọ́ ti kò si sí òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ṣugbọn bi nwọn ba gbadura si ibi yi, ti nwọn ba jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nitoriti iwọ pọn wọn loju. 27 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ ji, ati ti Israeli enia rẹ, nigbati iwọ ba ti kọ́ wọn li ọ̀na rere na, ninu eyiti nwọn o ma rìn: ki o si rọ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun awọn enia rẹ ni ini. 28 Bi ìyan ba mu ni ilẹ, bi àjakalẹ-arun ba wà, bi irẹ̀danu ba wà, tabi eṣú ti njẹrun, bi awọn ọta wọn ba yọ wọn li ẹnu ni ilẹ ilu wọn; oniruru ipọnju tabi oniruru àrun. 29 Adura ki adura, tabi ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ ti a ba ti ọdọ ẹnikẹni gbà, tabi ọdọ gbogbo Israeli enia rẹ, nigbati olukuluku ba mọ̀ ipọnju rẹ̀, ati ibanujẹ rẹ̀, ti o ba si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji siha ile yi: 30 Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ibugbe rẹ wá, ki o si dariji, ki o si san a fun olukuluku gẹgẹ bi gbogbo ọ̀na rẹ̀, bi iwọ ti mọ̀ ọkàn rẹ̀; (nitori iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn awọn ọmọ enia:) 31 Ki nwọn ki o le bẹ̀ru rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ, li ọjọ gbogbo ti nwọn o wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa. 32 Pẹlupẹlu niti alejo, ti kì iṣe inu Israeli, enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ òkere jade wá nitori orukọ nla rẹ, ati ọwọ agbara rẹ ati ninà apa rẹ; bi nwọn ba wá ti nwọn ba si gbadura siha ile yi: 33 Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejo na kepe ọ si; ki gbogbo enia aiye ki o le mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o si le ma bẹ̀ru rẹ̀, bi Israeli enia rẹ, ki nwọn ki o le mọ̀ pe orukọ rẹ li a npè mọ ile yi ti emi kọ́. 34 Bi awọn enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọta wọn li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, ti nwọn ba si gbadura si ọ, siha ilu yi, ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ: 35 Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wa, ki o si mu ọ̀ran wọn duro. 36 Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ (nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀,) bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le awọn ọta lọwọ, ti nwọn ba si kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ ti o jìna rére, tabi ti o wà nitosi. 37 Ṣugbọn, bi nwọn ba rò inu ara wọn wò, ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbekun lọ, ti nwọn ba si yipada, ti nwọn ba si gbadura si ọ li oko ẹrú wọn, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣìṣe, awa si ti ṣe buburu; 38 Bi nwọn ba si fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ li oko ẹrú wọn, si ibi ti a gbe kó wọn lọ, ti nwọn ba si gbadura siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ati siha ilu na ti iwọ ti yàn, ati siha ile na ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ: 39 Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wá, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si mu ọ̀ran wọn duro, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn enia rẹ jì ti nwọn ti da si ọ. 40 Nisisiyi Ọlọrun mi, jẹ ki oju rẹ ki o ṣí, ki o si tẹtisilẹ si adura si ihinyi. 41 Njẹ nisisiyi, dide, Oluwa Ọlọrun si ibi isimi rẹ, iwọ ati apoti agbara rẹ; jẹ ki a fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ, Oluwa Ọlọrun, ki o si jẹ ki awọn enia ayanfẹ rẹ ki o ma yọ̀ ninu ire. 42 Oluwa Ọlọrun, máṣe yi oju ẹni ororo rẹ pada: ranti ãnu fun Dafidi, iranṣẹ rẹ.

2 Kronika 7

Yíya Tẹmpili sí Mímọ́

1 BI Solomoni si ti pari adura igbà, iná bọ́ lati ọrun wá, o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ na run; ogo Oluwa si kún ile na. 2 Awọn alufa kò le wọ̀ inu ile Oluwa, nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa. 3 Gbogbo awọn ọmọ Israeli si ri bi iná na ti bọ́ silẹ, ati ogo Oluwa sori ile na, nwọn doju wọn bò ilẹ ti a fi okuta tẹ́, nwọn si tẹriba, nwọn si yìn Oluwa, wipe, Nitoriti o ṣeun; nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. 4 Ọba ati awọn enia si rubọ niwaju Oluwa. 5 Solomoni ọba si rubọ ẹgbã-mọkanla malu ati ọkẹ mẹfa agutan: bẹ̃ni ọba, ati gbogbo awọn enia yà ile Ọlọrun na si mimọ́. 6 Awọn alufa duro lẹnu iṣẹ wọn; awọn ọmọ Lefi pẹlu ohun-ọnà orin Oluwa, ti Dafidi ọba ti ṣe lati yìn Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai, nigbati Dafidi nkọrin iyìn nipa ọwọ wọn; awọn alufa si fùn ipè niwaju wọn, gbogbo Israeli si dide duro. 7 Solomoni si yà arin agbala na si mimọ́ ti mbẹ niwaju ile Oluwa: nitori nibẹ li o ru ẹbọ ọrẹ sisun, ati ọra ẹbọ alafia, nitori pẹpẹ idẹ ti Solomoni ti ṣe kò le gbà ọrẹ sisun, ati ọrẹ onjẹ ati ọ̀ra na. 8 Li akokò na pẹlu Solomoni se àse na ni ijọ meje, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ijọ enia nlanla, lati ìwọ Hamati titi de odò Egipti. 9 Ati li ọjọ kẹjọ nwọn ṣe apejọ mimọ́; nitori ti nwọn ṣe ìyasi-mimọ́ pẹpẹ na li ọjọ meje, ati àse na, ọjọ meje. 10 Ati li ọjọ kẹtalelogun oṣù keje, o rán awọn enia pada lọ sinu agọ wọn, pẹlu ayọ̀ ati inudidùn nitori ore-ọfẹ ti Oluwa ti fi hàn fun Dafidi, ati fun Solomoni, ati fun Israeli, enia rẹ̀.

Ọlọrun Tún Farahan Solomoni

11 Solomoni si pari ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ohun ti o wá si ọkàn Solomoni lati ṣe ninu ile Oluwa, ati ninu ile on tikararẹ̀, o si ṣe e jalẹ. 12 Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ. 13 Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi; 14 Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn. 15 Nisisiyi oju mi yio ṣí, eti mi yio si tẹ́ si adura ibi yi. 16 Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo. 17 Ati iwọ, bi iwọ o ba rìn niwaju mi bi Dafidi, baba rẹ ti rìn, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, bi iwọ o ba si ṣe akiyesi aṣẹ mi ati idajọ mi; 18 Nigbana ni emi o fi idi itẹ ijọba rẹ múlẹ̀, gẹgẹ bi emi ti ba Dafidi, baba rẹ dá majẹmu, wipe, a kì yio fẹ ẹnikan kù fun ọ ti yio ma ṣe akoso ni Israeli. 19 Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada, ti ẹ ba si kọ̀ aṣẹ mi ati ofin mi silẹ, ti emi ti gbé kalẹ niwaju nyin, ti ẹnyin ba si sin ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn; 20 Nigbana ni emi o fà wọn tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ni ilẹ ti emi ti fi fun wọn; ati ile yi, ti emi ti yà si mimọ́ fun orukọ mi, li emi o ta nù kuro niwaju mi, emi o si sọ ọ di owe, ati ọ̀rọ-ẹgan larin gbogbo orilẹ-ède. 21 Ati ile yi, ti o ga, yio di ohun iyanu fun gbogbo ẹni ti o gba ibẹ kọja; tobẹ̃ ti yio si wipe, ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi, ati si ile yi? 22 A o si dahùn wipe, Nitori ti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, Ẹniti o mu wọn ti ilẹ Egipti jade wá, ti nwọn si di ọlọrun miran mu, ti nwọn si bọ wọn, ti nwọn si sìn wọn: nitorina li o ṣe mu gbogbo ibi yi ba wọn.

2 Kronika 8

Àwọn Àsẹyọrí Solomoni

1 O si ṣe lẹhin ogun ọdun ninu eyi ti Solomoni kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀. 2 Ni Solomoni kọ́ ilu wọnni ti Huramu fi fun Solomoni, o si mu ki awọn ọmọ Israeli ki o ma gbe ibẹ. 3 Solomoni si lọ si Hamati-Soba, o si bori rẹ̀. 4 O si kọ́ Tadmori li aginju, ati gbogbo ilu iṣura ti o kọ́ ni Hamati. 5 O kọ́ Bet-Horoni ti òke pẹlu, ati Bet-Horoni ti isalẹ, ilu odi, pẹlu ogiri, ilẹkun, ati ọpa-idabu; 6 Ati Baalati, ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati gbogbo ilu kẹkẹ́, ati ilu ẹlẹṣin, ati gbogbo eyiti Solomoni fẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀. 7 Gbogbo awọn enia ti o kù ninu awọn ara Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Peresi, ati awọn Hifi ati awọn Jebusi, ti kì iṣe ti inu ọmọ Israeli. 8 Ninu awọn ọmọ wọn, ti a ṣẹkù silẹ lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò run kuro, awọn ni Solomoni bu iṣẹ-ìrú fun titi o fi di oni yi. 9 Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli ni Solomoni kò fi ṣe ọmọ-ọdọ fun iṣẹ rẹ̀; nitori awọn li ọga-ogun ati olori awọn onikẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. 10 Awọn wọnyi li olori awọn alaṣẹ Solomoni ọba, adọtalerugba ti nṣakoso lori awọn enia. 11 Solomoni si mu ọmọbinrin Farao gòke lati ilu Dafidi wá si ile ti o kọ́ fun u; nitori ti o wipe, Ni temi, obinrin kan kì yio gbe inu ile Dafidi, ọba Israeli, nitori mimọ́ ni ibi ti apoti-ẹri Oluwa ti de. 12 Nigbana ni Solomoni ru ẹbọ ọrẹ-sisun si Oluwa lori pẹpẹ Oluwa, ti o ti tẹ niwaju iloro na. 13 Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ. 14 O si yàn ipa awọn alufa, gẹgẹ bi ilana Dafidi baba rẹ̀, si ìsin wọn, ati awọn ọmọ Lefi si iṣẹ wọn, lati ma yìn, ati lati ma ṣe iranṣẹ niwaju awọn alufa, bi ilana ojojumọ: ati awọn adèna pẹlu ni ipa ti wọn li olukuluku ẹnu-ọ̀na: nitori bẹ̃ni Dafidi, enia Ọlọrun, ti pa a li aṣẹ. 15 Nwọn kò si yà kuro ninu ilana ọba nipa ti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi niti olukuluku ọ̀ran, ati niti iṣura. 16 Gbogbo iṣẹ Solomoni li a ti pese silẹ bayi de ọjọ ifi-ipilẹ ile Oluwa le ilẹ titi o fi pari. A si pari ile Oluwa. 17 Nigbana ni Solomoni lọ si Esion-Geberi, ati si Eloti, ati si eti okun ni ilẹ Edomu. 18 Huramu si fi ọkọ̀ ranṣẹ si i, nipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ ti o moye okun; nwọn si ba awọn iranṣẹ Solomoni lọ si Ofiri, lati ibẹ ni nwọn mu ãdọta-le-ni-irinwo talenti wura wá, nwọn si mu wọn tọ̀ Solomoni ọba wá.

2 Kronika 9

Ìbẹ̀wò Ọbabinrin Ṣeba sí Solomoni

1 NIGBATI ayaba Ṣeba gbọ́ òkiki Solomoni, o wá lati fi àlọ dan Solomoni wò ni Jerusalemu, pẹlu ẹgbẹ́ nlanla, ati ibakasiẹ ti o ru turari, ati wura li ọ̀pọlọpọ ati okuta iyebiye; nigbati o si de ọdọ Solomoni, o ba a sọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀. 2 Solomoni si dahùn gbogbo ibère rẹ̀: kò si si ohun kan ti o pamọ fun Solomoni ti kò sọ fun u, 3 Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́, 4 Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati aṣọ-wiwọ̀ wọn; ati awọn agbọti rẹ̀ pẹlu aṣọ-wiwọ̀ wọn, ati àtẹgun ti o mba gòke lọ si ile Oluwa; kò si kù agbara kan ninu rẹ̀ mọ. 5 O si wi fun ọba pe, otitọ ni ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ, ati ọgbọ́n rẹ: 6 Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ wọn gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri i; si kiyesi i, a kò rò idaji titobi ọgbọ́n rẹ fun mi; nitori ti iwọ kọja òkiki ti mo ti gbọ́. 7 Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún si ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro nigbagbogbo niwaju rẹ, ti o si ngbọ́ ọgbọ́n rẹ. 8 Olubukún li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori itẹ́ rẹ̀ lati ṣe ọba fun Oluwa Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israeli lati fi idi wọn kalẹ lailai, nitorina ni o ṣe fi ọ jọba lori wọn, lati ṣe idajọ ati otitọ. 9 O si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọpọlọpọ, ati okuta iyebiye: bẹ̃ni kò ti isi iru turari gẹgẹ bi eyiti ayaba Ṣeba fun Solomoni ọba. 10 Awọn iranṣẹ Huramu pẹlu, ati awọn iranṣẹ Solomoni ti o mu wura Ofiri wá, si mu igi-algumu, ati okuta iyebiye wá pẹlu. 11 Ọba si fi igi-algumu na ṣe àtẹgun ni ile Oluwa, ati ni ile ọba, ati duru ati ohun ọ̀na-orin fun awọn akọrin: a kò si ri iru bẹ̃ ri ni ilẹ Juda. 12 Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba li ohun gbogbo ti o wù u, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti o mu wa fun ọba. Bẹ̃ni o yipada, o si lọ si ilẹ rẹ̀, ati on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

Ọrọ̀ Solomoni Ọba

13 Njẹ nisisiyi ìwọn wura ti o de fun Solomoni li ọdun kan ni ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura. 14 Laika eyiti awọn oniṣowo ati awọn èro mu wá. Ati awọn ọba Arabia, ati awọn bãlẹ ilẹ na nmu wura ati fadakà tọ̀ Solomoni wá. 15 Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: asà kan gba ẹgbẹta ṣekeli wura lilù. 16 Ọdunrun apata wura lilù li o si ṣe; apata kan gbà ọ̃dunrun ṣekeli wura: ọba si fi wọn sinu ile igbo Lebanoni. 17 Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin nla kan, o si fi wura daradara bò o. 18 Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na. 19 Kiniun mejila si duro lori atẹgun mẹfẹfa na, ni iha ekini ati ni iha ekeji. A kò ṣe iru rẹ̀ ri ni gbogbo ijọba. 20 Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni, wura daradara ni: kò si ti fadakà; a kò kà fadakà si nkankan li ọjọ Solomoni. 21 Nitori awọn ọkọ̀ ọba nlọ si Tarṣiṣi pẹlu awọn iranṣẹ Huramu; ẹ̃kan li ọdun mẹta li awọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ide, nwọn nmu wura, ati fadakà, ati ehin-erin, ati inaki, ati ẹiyẹ-ologe wá. 22 Solomoni ọba si tobi jù gbogbo ọba aiye lọ li ọrọ̀ ati li ọgbọn. 23 Gbogbo awọn ọba aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn. 24 Olukuluku si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadakà ati ohun-elo wura, ati aṣọ ibora, ihamọra, ati turari, ẹṣin, ati ibaka, iye kan li ọdọdun. 25 Solomoni si ni ẹgbaji ile fun ẹṣin ati kẹkẹ́, ati ẹgbafa ẹlẹṣin, ti o fi si awọn ilu kẹkẹ́, ati ọdọ ọba ni Jerusalemu. 26 O si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò (Euferate) titi de ilẹ awọn ara Filistia ati de àgbegbe Egipti. 27 Ọba si sọ fadakà dabi okuta ni Jerusalemu, ati igi-kedari li o si ṣe bi sikamore, ti o wà ni pẹtẹlẹ li ọ̀pọlọpọ. 28 Nwon si mu ẹṣin tọ̀ Solomoni lati Egipti wá, ati lati ilẹ gbogbo.

Ìjọba Solomoni Ní Ṣókí

29 Ati iyokù iṣe Solomoni ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kọ ha kọ wọn sinu iwe Natani woli, ati sinu asọtẹlẹ Ahijah, ara Ṣilo, ati sinu iran Iddo, ariran, sipa Jeroboamu, ọmọ Nebati. 30 Solomoni si jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli li ogoji ọdun. 31 Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 10

Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Àríwá Dìtẹ̀

1 REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu: nitori gbogbo Israeli wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba. 2 O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati gbọ́, on si wà ni Egipti nibiti o ti salọ kuro niwaju Solomoni ọba, ni Jeroboamu pada ti Egipti wá. 3 Nwọn si ranṣẹ pè e. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo Israeli wá, nwọn si ba Rehoboamu sọ̀rọ, wipe, 4 Baba rẹ mu ki àjaga wa ki o wuwo: njẹ nisisiyi iwọ ṣẹkù kuro ninu ìsin baba rẹ ti o nira, ati àjaga wuwo rẹ̀ ti o fi bọ̀ wa lọrùn, awa o si ma sìn ọ. 5 On si wi fun wọn pe, Ẹ tun pada tọ̀ mi wá lẹhin ijọ mẹta. Awọn enia na si lọ. 6 Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba ti o ti nduro niwaju Solomoni baba rẹ̀; nigbati o wà lãye dá imọran, wipe, imọran kili ẹnyin dá lati da awọn enia yi lohùn? 7 Nwọn si ba a sọ̀rọ pe, bi iwọ ba ṣe ire fun enia yi, ti iwọ ba ṣe ohun ti o wù wọn, ti o ba si sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ nigbagbogbo. 8 Ṣugbọn o kọ̀ imọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti o dàgba pẹlu rẹ̀ damọran, ti o duro niwaju rẹ̀. 9 On si wi fun wọn pe, Imọran kili ẹnyin dá, ki awa ki o le da awọn enia yi lohùn, ti o ba mi sọ̀rọ, wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi bọ̀ wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ? 10 Awọn ipẹrẹ ti a tọ́ pẹlu rẹ̀ si sọ fun u wipe, Bayi ni iwọ o da awọn enia na li ohùn ti o sọ fun ọ, wipe, Baba rẹ mu àjaga wa di wuwo, ṣugbọn iwọ ṣe e ki o fẹrẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o wi fun wọn, Ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ. 11 Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin. 12 Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta. 13 Nigbana ni ọba da wọn li ohùn akọ; Rehoboamu ọba si kọ̀ imọran awọn àgbagba silẹ. 14 O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin. 15 Bẹ̃ni ọba kò si fetisi ti awọn enia na: nitori ṣiṣẹ ọ̀ran na lati ọwọ Ọlọrun wá ni, ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti o sọ nipasẹ Ahijah, ara Ṣilo fun Jeroboamu, ọmọ Nebati. 16 Nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kọ̀ lati fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba lohùn, wipe, Ipin kili a ni ninu Dafidi? awa kò si ni ini kan ninu ọmọ Jesse: Israeli, olukuluku sinu agọ rẹ̀: nisisiyi Dafidi, mã bojuto ile rẹ. Bẹ̃ni gbogbo Israeli lọ sinu agọ wọn, 17 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn. 18 Nigbana ni Rehoboamu ọba ran Hadoramu ti iṣe olori iṣẹ-irú; awọn ọmọ Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Ṣugbọn Rehoboamu ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀ lati salọ si Jerusalemu. 19 Bẹ̃ni Israeli si ya kuro lọdọ ile Dafidi titi o fi di oni yi.

2 Kronika 11

Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya

1 NIGBATI Rehoboamu si de Jerusalemu o kó ile Juda ati Benjamini jọ, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba Israeli jà, ki o le mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu. 2 Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ Ṣemaiah, enia Ọlọrun, wá, wipe, 3 Sọ fun Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo Israeli ni Juda ati Benjamini, wipe, 4 Bayi li Oluwa wi, ẹnyin kò gbọdọ gòke lọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ki olukuluku pada si ile rẹ̀: nitori ọ̀ran yi lati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbà ọ̀rọ Oluwa gbọ́, nwọn si yipada kuro lati lọ iba Jeroboamu.

Rehoboamu Mọ Odi yí Àwọn Ìlú Ká

5 Rehoboamu si ngbe Jerusalemu, o si kọ́ ilu olodi ni Juda. 6 O kọ́ Betlehemu pẹlu, ati Etamu, ati Tekoa, 7 Ati Bet-Suri, ati Soko, ati Adullamu, 8 Ati Gati, ati Mareṣa, ati Sifu, 9 Ati Adoraimu, ati Lakiṣi, ati Aseki, 10 Ati Sora, ati Aijaloni, ati Hebroni, ti o wà ni Juda ati ni Benjamini, awọn ilu olodi. 11 O si mu awọn ilu olodi lagbara, o si fi awọn balogun sinu wọn ati akojọ onjẹ, ati ororo ati ọti-waini. 12 Ati ni olukuluku ilu li o fi asà ati ọ̀kọ si, o si mu wọn lagbara gidigidi, o si ni Juda ati Benjamini labẹ rẹ̀. 13 Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ti o wà ni gbogbo Israeli, tọ̀ ọ lọ lati gbogbo ibugbe wọn wá. 14 Nitori ti awọn ọmọ Lefi fi ìgberiko wọn silẹ, ati ini wọn, nwọn si lọ si Juda ati Jerusalemu: nitori Jeroboamu ati awọn ọmọ rẹ̀ ti le wọn kuro lati ma ṣiṣẹ alufa fun Oluwa. 15 O si yàn awọn alufa fun ibi-giga wọnni, ati fun awọn ere-obukọ ati fun ẹ̀gbọrọ-malu ti o ti ṣe. 16 Lẹhin wọn iru awọn ti o fi ọkàn wọn si ati wá Oluwa Ọlọrun Israeli lati inu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli wá, si wá si Jerusalemu, lati ṣe irubọ si Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn. 17 Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.

Àwọn Ìdílé Rehoboamu

18 Rehoboamu si mu Mahalati, ọmọbinrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, li aya, ati Abihaili, ọmọbinrin Eliabi, ọmọ Jesse: 19 Ẹniti o bi ọmọkunrin wọnyi fun u; Jeuṣi, ati Ṣamariah, ati Sahamu. 20 Ati lẹhin rẹ̀, o mu Maaka, ọmọbinrin Absalomu ti o bi Abijah fun u, ati Attai, ati Sisa, ati Ṣelomiti. 21 Rehoboamu si fẹran Maaka ọmọbinrin Absalomu, jù gbogbo awọn aya rẹ̀ ati àle rẹ̀ lọ: (nitoriti o ni aya mejidilogun, ati ọgọta àle: o si bi ọmọkunrin mejidilọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin). 22 Rehoboamu si ṣe Abijah, ọmọ Maaka, li olori lati ṣe olori ninu awọn arakunrin rẹ̀: nitori ti o rò lati fi i jọba. 23 On si huwà ọlọgbọ́n, o si tú ninu gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ka si gbogbo ilẹ Juda ati Benjamini, si olukuluku ilu olodi: o si fun wọn li onjẹ li ọ̀pọlọpọ. O si fẹran ọ̀pọlọpọ obinrin.

2 Kronika 12

Àwọn Ará Ijipti Gbógun ti Juda

1 O si ṣe, nigbati Rehoboamu ti fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ ti o si ti mu ara rẹ̀ le, o kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀. 2 O si ṣe ni ọdun karun Rehoboamu ọba, ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, gòke wá si Jerusalemu, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa. 3 Pẹlu ẹgbẹfa kẹkẹ́, ati ọkẹ́ mẹta ẹlẹṣin: awọn enia ti o ba a ti Egipti wá kò niye; awọn ara Libia, awọn ara Sukki, ati awọn ara Etiopia. 4 O si kọ́ awọn ilu olodi ti iṣe ti Juda, o si wá si Jerusalemu. 5 Nigbana ni Ṣemaiah, woli, tọ̀ Rehoboamu wá, ati awọn ijoye Juda, ti o kojọ pọ̀ si Jerusalemu nitori Ṣiṣaki, o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, enyin ti kọ̀ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ Ṣiṣaki. 6 Nigbana li awọn ijoye Israeli ati ọba rẹ̀ ara wọn silẹ; nwọn si wipe: Oluwa li olododo! 7 Nigbati Oluwa ri pe nwọn rẹ̀ ara wọn silẹ, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Ṣemaiah wá, wipe, Nwọn ti rẹ̀ ara wọn silẹ; nitorina emi kì o run wọn, ṣugbọn emi o fun wọn ni igbala diẹ: a kì yio dà ibinu mi sori Jerusalemu nipa ọwọ Ṣiṣaki. 8 Ṣugbọn nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ̀: ki nwọn ki o le mọ̀ ìsin mi, ati ìsin ijọba ilẹ wọnni. 9 Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe. 10 Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn le ọwọ olori ẹṣọ ti ntọju ọ̀na ile ọba. 11 O si ṣe, nigbakugba ti ọba ba si wọ̀ ile Oluwa lọ, awọn ẹṣọ a de, nwọn a si kó wọn wá, nwọn a si kó wọn pada sinu iyara ẹṣọ. 12 Nigbati o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ibinu Oluwa yipada kuro lọdọ rẹ̀, ti kò fi run u patapata: ni Juda pẹlu, ohun rere si mbẹ.

Ìjọba Rehoboamu ní ṣókí

13 Bẹ̃ni Rehoboamu ọba mu ara rẹ̀ le ni Jerusalemu, o si jọba: nitori Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹtadinlogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. 14 O si ṣe buburu, nitori ti kò mura ọkàn rẹ̀ lati wá Oluwa. 15 Njẹ iṣe Rehoboamu, ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kò ha kọ wọn sinu iwe Ṣemaiah, woli, ati ti Iddo, ariran, nipa iwe itan idile? Ọtẹ si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu nigbagbogbo. 16 Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi: Abijah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 13

Ogun láàrin Abija ati Jeroboamu

1 LI ọdun kejidilogun Jeroboamu, ọba, ni Abijah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda. 2 O jọba li ọdun mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Mikaiah ọmọbinrin Urieli ti Gibea, ọtẹ si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu. 3 Abijah si fi awọn alagbara akọni ologun dì ogun na, ani ogún ọkẹ́ enia ti a yàn, Jeroboamu pẹlu si fi ogoji ọkẹ enia ti a yàn, awọn alagbara akọni enia tẹ́ ogun si i. 4 Abijah si duro lori oke Semaraimu, ti o wà li òke Efraimu, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, Jeroboamu ati gbogbo Israeli! 5 Kò ha tọ́ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe: Oluwa Ọlọrun Israeli fi ijọba lori Israeli fun Dafidi lailai, ani fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa majẹmu iyọ̀? 6 Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi dide, o si ṣọ̀tẹ si oluwa rẹ̀. 7 Awọn enia lasan si ko ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀, awọn ọmọ ẹni buburu, nwọn si mu ara wọn le si Rehoboamu, ọmọ Solomoni, nigbati Rehoboamu wà li ọdọmọde ti inu rẹ̀ si rọ̀, ti kò si le kò wọn loju. 8 Ati nisisiyi ẹnyin rò lati kò ijọba Oluwa loju li ọwọ ọmọ Dafidi; ọ̀pọlọpọ si li ẹnyin, ati pẹlu nyin awọn ẹgbọrọmalu wura ti Jeroboamu ṣe li ọlọrun fun nyin. 9 Ẹnyin kò ha ti lé awọn alufa Oluwa jade, awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi, ẹnyin si ti ṣe awọn alufa fun ara nyin, gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède ilẹ miran? bẹ̃ni ẹnikẹni ti o ba wá, ti ọwọ rẹ kún pẹlu ọdọ-akọ-malu ati àgbo meje, on na le ma ṣe alufa awọn ti kì iṣe ọlọrun. 10 Ṣugbọn bi o ṣe ti wa ni, Oluwa li Ọlọrun wa, awa kò si kọ̀ ọ silẹ ati awọn alufa, ti nṣe iranṣẹ fun Oluwa, ani awọn ọmọ Aaroni ati awọn ọmọ Lefi ninu iṣẹ wọn. 11 Nwọn si nsun ọrẹ-ẹbọ sisun ati turari didùn li orowurọ ati li alalẹ si Oluwa: àkara ifihan pẹlu ni nwọn si ntò lori tabili mimọ́; ati ọpa fitila wura pẹlu fitila wọn, lati ma jó lalalẹ; nitori ti awa npa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wa mọ́; ṣugbọn ẹnyin kọ̀ ọ silẹ. 12 Si kiyesi i, Ọlọrun tikararẹ̀ si wà pẹlu wa li Olori wa, ati awọn alufa rẹ̀ pẹlu ipè didún ijaiya lati dún si nyin, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ máṣe ba Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin jà; nitori ẹ kì yio ṣe rere. 13 Ṣugbọn Jeroboamu mu ki ogun-ẹ̀hin ki o bù wọn li ẹhin: bẹ̃ni nwọn mbẹ niwaju Juda, ati ogun-ẹhin na si mbẹ lẹhin wọn. 14 Nigbati Juda si bojuwo ẹhin, si kiyesi i, ogun mbẹ niwaju ati lẹhin: nwọn si ke pè Oluwa, awọn alufa si fún ipè. 15 Olukuluku, ọkunrin Juda si hó: o si ṣe, bi awọn ọkunrin Juda si ti hó, ni Ọlọrun kọlu Jeroboamu ati gbogbo Israeli niwaju Abijah ati Juda. 16 Awọn ọmọ Israeli si sa niwaju Juda: Ọlọrun si fi wọn le wọn lọwọ. 17 Abijah ati awọn enia rẹ̀ si pa ninu wọn li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni ọkẹ mẹdọgbọn ọkunrin ti a yàn ṣubu ni pipa ninu Israeli. 18 Bayi li a rẹ̀ awọn ọmọ Israeli silẹ li akoko na, awọn ọmọ Juda si bori nitori ti nwọn gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn. 19 Abijah si lepa Jeroboamu, o si gbà ilu lọwọ rẹ̀, Beteli pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Jeṣana pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Efraimu pẹlu awọn ilu rẹ̀. 20 Bẹ̃ni Jeroboamu kò si tun li agbara mọ li ọjọ Abijah: Oluwa si lù u, o si kú. 21 Abijah si di alagbara, o si gbe obinrin mẹtala ni iyawo, o si bi ọmọkunrin mejilelogun, ati ọmọbinrin mẹrindilogun. 22 Ati iyokù iṣe Abijah, ati iwà rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, a kọ wọn sinu iwe-itumọ Iddo, woli.

2 Kronika 14

Asa Ọba Ṣẹgun Àwọn Ará Sudani

1 Bẹ̃ni Abijah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Asa ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Li ọjọ rẹ̀, ilẹ na wà li alafia li ọdun mẹwa. 2 Asa si ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀. 3 Nitori ti o mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, ati ibi giga wọnni, o si wó awọn ere palẹ, o si bẹ ere-oriṣa wọn lulẹ: 4 O si paṣẹ fun Juda lati ma wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, ati lati ma pa aṣẹ ati ofin rẹ̀ mọ́. 5 O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀. 6 O si kọ́ ilu olodi wọnni ni Juda, nitoriti ilẹ na ni isimi, on kò si ni ogun li ọdun wọnni; nitori Oluwa ti fun wọn ni isimi. 7 O si sọ fun Juda pe, Ẹ jẹ ki a kọ́ ilu wọnni, ki a si mọdi yi wọn ka, ati ile-iṣọ, ilẹkun ati ọpa-idabu, nigbati ilẹ na si wà niwaju wa, nitori ti awa ti wá Oluwa Ọlọrun wa, awa ti wá a, on si ti fun wa ni isimi yikakiri. Bẹ̃ni nwọn kọ́ wọn, nwọn si ṣe rere. 8 Asa si ni ogun ti ngbé asà ati ọ̀kọ, ọkẹ mẹdogun lati inu Juda wá, ati lati inu Benjamini wá, ọkẹ mẹrinla ti ngbé apata ati ti nfa ọrun: gbogbo wọnyi si ni akọni ogun. 9 Sera, ara Etiopia, si jade si wọn, pẹlu ãdọta ọkẹ enia, ati ọ̃dunrun kẹkẹ́; nwọn wá si Mareṣa. 10 Asa si jade tọ̀ ọ, nwọn si tẹ ogun li afonifoji Sefata lẹba Mareṣa. 11 Asa si ke pe Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, Oluwa! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ràn alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, Oluwa Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹ le ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọ̀pọlọpọ yi lọ, Oluwa, iwọ li Ọlọrun wa; máṣe jẹ ki enia ki o bori rẹ, 12 Bẹ̃li Oluwa kọlù awọn ara Etiopia niwaju Asa, ati niwaju Juda: awọn ara Etiopia si sa. 13 Ati Asa ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ lepa wọn de Gerari: a si bi awọn ara Etiopia ṣubu ti ẹnikan kò tun wà li ãye; nitori ti a ṣẹ́ wọn niwaju Oluwa ati niwaju ogun rẹ̀; nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ikogun lọ. 14 Nwọn si kọlu gbogbo ilu yikakiri Gerari: nitori ti ẹ̀ru Oluwa bà wọn, nwọn si kó gbogbo ilu na, nitori ikógun pọ̀ rekọja ninu wọn. 15 Nwọn si kọlù awọn agbo-ẹran-ọsin, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ agutan ati ibakasiẹ lọ, nwọn si pada wá si Jerusalemu.

2 Kronika 15

Asa Ṣe Àtúnṣe

1 ẸMI Ọlọrun si wá si ara Asariah, ọmọ Odedi: 2 O si jade lọ ipade Asa, o si wi fun u pe, Ẹ gbọ́ temi, Asa, ati gbogbo Juda ati Benjamini! Oluwa pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rẹ̀, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀ ọ, on o si kọ̀ nyin. 3 Njẹ ọjọ pupọ ni Israeli ti wà laisìn Ọlọrun otitọ, ati laini alufa ti nkọni, ati laini ofin. 4 Ṣugbọn nwọn yipada si Oluwa. Ọlọrun Israeli, ninu wahala wọn, nwọn si ṣe awari rẹ̀, nwọn si ri i. 5 Ati li ọjọ wọnni alafia kò si fun ẹniti o njade, tabi fun ẹniti nwọle, ṣugbọn ibanujẹ pupọ li o wà lori gbogbo awọn olugbe ilẹ wọnni. 6 Orilẹ-ède si kọlù orilẹ-ède, ati ilu si ilu: nitori ti Ọlọrun fi oniruru ipọnju bà wọn ninu jẹ. 7 Ṣugbọn ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ ọwọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ère. 8 Nigbati Asa gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ati asọtẹlẹ Odedi woli, o mu ara le, o si mu awọn ohun irira kuro lati inu gbo-gbo ilẹ Juda ati Benjamini, ati lati inu ilu ti o ti gbà lati oke Efraimu, o si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, ti o wà niwaju iloro Oluwa. 9 O si kó gbogbo Juda ati Benjamini jọ, ati awọn alejo ti o pẹlu wọn lati inu Efraimu ati Manasse, ati lati inu Simeoni wá: nitori ti nwọn ya li ọ̀pọlọpọ sọdọ rẹ̀ lati inu Israeli wá, nigbati nwọn ri pe, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀. 10 Bẹ̃ni nwọn kó ara wọn jọ si Jerusalemu, li oṣù kẹta, li ọdun kẹdogun ijọba Asa. 11 Nwọn si fi ninu ikógun ti nwọn kó wá, rubọ si Oluwa li ọjọ na, ẹ̃dẹgbãrin akọ-malu ati ẹ̃dẹgbãrin agutan. 12 Nwọn si tun dá majẹmu lati wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, tinutinu wọn ati tọkàntọkàn wọn. 13 Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin. 14 Nwọn si fi ohùn rara bura fun Oluwa, ati pẹlu ariwo, ati pẹlu ipè ati pẹlu fère. 15 Gbogbo Juda si yọ̀ si ibura na: nitoriti nwọn fi tinu-tinu wọn bura, nwọn si fi gbogbo ifẹ inu wọn wá a; nwọn si ri i: Oluwa si fun wọn ni isimi yikakiri. 16 Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni. 17 Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro ni Israeli: kiki ọkàn Asa wà ni pipé li ọjọ rẹ̀ gbogbo. 18 O si mu ohun mimọ́ wọnni ti baba rẹ̀, ati ohun mimọ́ wọnni ti on tikararẹ̀ wá sinu ile Ọlọrun, fadakà, wura, ati ohun-elo wọnni. 19 Ogun kò si mọ titi di ọdun karundilogoji ọba Asa.

2 Kronika 16

Ìyọnu De bá Israẹli

1 LI ọdun kẹrindilogoji ijọba Asa, Baaṣa, ọba Israeli, gòke wá si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má ba jẹ ki ẹnikan ki o jade, tabi ki o wọle tọ̀ Asa, ọba Juda lọ. 2 Nigbana ni Asa mu fadakà ati wura jade lati inu iṣura ile Oluwa wá, ati ile ọba, o si ranṣẹ si Benhadadi, ọba Siria, ti ngbe Damasku, wipe, 3 Majẹmu kan wà larin temi tirẹ, bi o ti wà lãrin baba mi ati baba rẹ; kiyesi i, mo fi fadakà ati wura ranṣẹ si ọ; lọ, bà majẹmu ti o ba Baaṣa, ọba Israeli dá jẹ, ki o le lọ kuro lọdọ mi. 4 Benhadadi si gbọ́ ti Asa ọba, o si rán awọn olori ogun rẹ̀ si ilu Israeli wọnni, nwọn si kọlù Ijoni, ati Dani, ati Abel-Maimu, ati gbogbo ilu iṣura Naftali. 5 O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o ṣiwọ atikọ́ Rama, o si dá iṣẹ rẹ̀ duro. 6 Ṣugbọn Asa ọba kó gbogbo Juda jọ; nwọn si kó okuta ati igi Rama lọ, eyiti Baaṣa nfi kọ́le; o si fi kọ́ Geba ati Mispa.

Wolii Hanani

7 Li àkoko na Hanani, ariran, wá sọdọ Asa, ọba Juda, o si wi fun u pe, Nitoriti iwọ gbẹkẹle ọba Siria, iwọ kò si gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun rẹ, nitorina ni ogun ọba Siria ṣe bọ́ lọwọ rẹ. 8 Awọn ara Etiopia ati awọn ara Libia kì iha ise ogun nla, pẹlu ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin? ṣugbọn nitoriti iwọ gbẹkẹle Oluwa, on fi wọn le ọ lọwọ. 9 Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà. 10 Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na.

Òpin Ìjọba Asa

11 Si kiyesi i, iṣe Asa ti iṣaju ati ti ikẹhin, wò o, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli. 12 Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun. 13 Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, o si kú li ọdun kọkanlelogoji ijọba rẹ̀. 14 Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.

2 Kronika 17

Jehoṣafati di Ọba

1 JEHOṢAFATI, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀, o si mu ara rẹ̀ le si Israeli. 2 O si fi ogun sinu gbogbo ilu olodi Juda, o si fi ẹgbẹ-ogun si ilẹ Juda ati sinu ilu Efraimu wọnni, ti Asa baba rẹ̀ ti gbà. 3 Oluwa si wà pẹlu Jehoṣafati, nitoriti o rìn ninu ọ̀na iṣaju Dafidi, baba rẹ̀, kò si wá Baalimu: 4 Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli. 5 Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ. 6 Ọkàn rẹ̀ si gbé soke li ọ̀na Oluwa: pẹlupẹlu o si mu ibi giga wọnni ati ere-oriṣa kuro ni Juda. 7 Ati li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o ranṣẹ si awọn ijoye rẹ̀, ani si Benhaili ati si Obadiah ati Sekariah, ati si Netaneeli, ati si Mikaiah, lati ma kọ́ni ninu ilu Juda wọnni. 8 Ati pẹlu wọn, o rán awọn ọmọ Lefi, ani Ṣemaiah, ati Netaniah, ati Sebadiah, ati Asaheli, ati Ṣemiramotu, ati Jehonatani, ati Adonijah, ati Tobijah, ati Tob-Adonijah, awọn ọmọ Lefi; ati pẹlu wọn Eliṣama, ati Jehoramu, awọn alufa. 9 Nwọn si kọ́ni ni Juda, nwọn si ni ofin Oluwa pẹlu wọn, nwọn si lọ kakiri ja gbogbo ilu Juda, nwọn si kọ́ awọn enia.

Títóbi Jehoṣafati

10 Ẹ̀ru Oluwa si ba gbogbo ijọba ilẹ na, ti o wà yikakiri Juda, tobẹ̃ ti nwọn kò ba Jehoṣafati jagun kan. 11 Ati ninu awọn ara Filistia mu ọrẹ fun Jehoṣafati wá, ati fadakà owo ọba: awọn ara Arabia si mu ọwọ́-ẹran fun u wá, ẹgbãrin àgbo o di ọ̃dunrun, ati ẹgbãrin obukọ di ọ̃dunrun. 12 Jehoṣafati si npọ̀ si i gidigidi: o si kọ́ ile olodi, ati ilu iṣura ni Juda. 13 O si ni iṣura pupọ ni ilu Juda; ati awọn jagunjagun, awọn alagbara akọni ọkunrin ti o wà ni Jerusalemu. 14 Wọnyi ni iye wọn gẹgẹ bi ile baba wọn: Ninu Juda, awọn olori ẹgbẹgbẹrun; Adna, olori, ati pẹlu rẹ̀, ọkẹ́ mẹ̃dogun alagbara akọni ọkunrin. 15 Ati atẹle rẹ̀ ni Jehohanani olori, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹrinla ọkunrin. 16 Ati atẹle rẹ̀ ni Amasiah, ọmọ Sikri, ti o fi tinutinu fi ara rẹ̀ fun Oluwa; ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹwa alagbara akọni ọkunrin. 17 Ati ninu Benjamini; Eliada alagbara akọni ọkunrin, ati pẹlu rẹ̀ awọn enia ti nfi ọrun ati apata hamọra, ọkẹ mẹwa. 18 Ati atẹle rẹ̀ ni Jehosabadi, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹsan, ti o mura silẹ de ogun. 19 Wọnyi nduro tì ọba, li aika awọn ti ọba fi sinu ilu olodi ni gbogbo Juda.

2 Kronika 18

Wolii Mikaya Kìlọ̀ fún Ahabu

1 JEHOṢAFATI si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ, o si ba Ahabu dá ana. 2 Lẹhin ọdun melokan, on sọ̀kalẹ tọ Ahabu lọ si Samaria. Ahabu si pa agutan ati malu fun u li ọ̀pọlọpọ ati fun awọn enia ti o pẹlu rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati ba a gòke lọ si Ramoti-Gileadi. 3 Ahabu ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati ọba Juda pe, Iwọ o ha ba mi lọ si Ramoti-Gileadi bi? On si da a li ohùn wipe, Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ; awa o pẹlu rẹ li ogun na. 4 Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa loni. 5 Nitorina ọba Israeli kó awọn woli jọ, irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki awa ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Gòke lọ; Ọlọrun yio si fi i le ọba lọwọ. 6 Ṣugbọn Jehoṣafati wipe, kò si woli Oluwa nihin pẹlu, ti awa ìba bère lọwọ rẹ̀? 7 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan mbẹ sibẹ lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀: nitoriti kò jẹ sọ asọtẹlẹ rere si mi lai, bikòṣe ibi nigbagbogbo: eyini ni Mikaiah, ọmọ Imla. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba ki o má sọ bẹ̃. 8 Ọba Israeli si pè ìwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah ọmọ Imla, ki o yara wá. 9 Ati ọba Israeli, ati Jehoṣafati, ọba Juda joko, olukuluku lori itẹ rẹ̀, nwọn si wọ aṣọ igunwa wọn, nwọn si joko ni ita ẹnubọde Samaria; gbogbo awọn woli si nsọ asọtẹlẹ niwaju wọn. 10 Sedekiah ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn awọn ara Siria titi iwọ o fi run wọn. 11 Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe, Gòke lọ si Ramoti-Gileadi, iwọ o ṣe rere; Oluwa yio si fi i le ọba lọwọ. 12 Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah si wi fun u pe, Kiye si i, awọn woli fi ẹnu kan sọ rere fun ọba: Njẹ emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọkan ninu ti wọn, ki o si sọ rere. 13 Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ani, eyiti Ọlọrun mi ba wi li emi o sọ. 14 Nigbati o si tọ̀ ọba wá, ọba sọ fun u pe, Mikaiah, ki awa ki o lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? O si wipe, Ẹ lọ, ẹnyin o si ṣe rere, a o si fi wọn le nyin lọwọ. 15 Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bú ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikòṣe ọ̀rọ otitọ li orukọ Oluwa? 16 On si wipe, Emi ri gbogbo Israeli fọnka kiri lori awọn òke, bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa: jẹ ki nwọn ki o pada, olukuluku si ile rẹ̀ li alafia. 17 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò ti wi fun ọ pe: on kì isọtẹlẹ rere si mi, bikòṣe ibi? 18 Mikaiah si wipe, Nitorina, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun ọrun duro lapa ọtún ati lapa òsi rẹ̀. 19 Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ọba Israeli, ki o le gòke lọ ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ekini si sọ bayi, ekeji si sọ miran. 20 Nigbana ni ẹmi na jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a. Oluwa si wi fun u pe, Bawo? 21 On si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. Oluwa si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃ na. 22 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ. 23 Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana, sunmọ ọ, o si lù Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà kọja lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ. 24 Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o wọ inu iyẹwu de inu iyẹwu lọ ifi ara rẹ pamọ́, 25 Nigbana ni ọba Israeli wipe, Ẹ mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba. 26 Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi, ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi ọnjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia. 27 Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ọdọ mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!

Ikú Ahabu

28 Bẹ̃li ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, si gòke lọ si Ramoti-Gileadi. 29 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ìja; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Bẹ̃li ọba Israeli si pa aṣọ dà: nwọn si lọ si oju ìja. 30 Ṣugbọn ọba Siria ti paṣẹ fun awọn olori kẹkẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Ẹ máṣe ba ewe tabi àgba jà, bikòṣe ọba Israeli nikan. 31 O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ ri Jehoṣafati, ni nwọn wipe eyi li ọba Israeli, nitorina nwọn yi i ka lati ba a jà: ṣugbọn Jehoṣafati kigbe, Oluwa si ràn a lọwọ: Ọlọrun si yi wọn pada kuro lọdọ rẹ̀. 32 O si ṣe, bi awọn olori kẹkẹ́ ti woye pe kì iṣe ọba Israeli, nwọn yipada kuro lẹhin rẹ̀. 33 Ọkunrin kan si fa ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin, o si wi fun olutọju kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ rẹ pada, ki o mu mi jade kuro loju ìja; nitoriti mo gbọgbẹ́. 34 Ija na si pọ̀ li ọjọ na: pẹlupẹlu ọba Israeli duro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ kọju si awọn ara Siria titi di aṣãlẹ: o si kú li akokò ìwọ õrun.

2 Kronika 19

Wolii Kan Bá Jehoṣafati Wí

1 JEHOṢAFATI, ọba Juda, si pada lọ si ile rẹ̀ ni Jerusalemu li alafia. 2 Jehu, ọmọ Hanani, ariran, si jade lọ ipade rẹ̀, o si wi fun Jehoṣafati pe, iwọ o ha ma ràn enia buburu lọwọ, iwọ o si fẹran awọn ti o korira Oluwa? njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ Oluwa. 3 Ṣugbọn a ri ohun rere ninu rẹ, pe, nitori ti iwọ ti mu awọn ere-oriṣa kuro ni ilẹ na, ti o si mura ọkàn rẹ lati wá Ọlọrun.

Jehoṣafati Ṣe Àtúnṣe

4 Jehoṣafati si ngbe Jerusalemu: o nlọ, o mbọ̀ lãrin awọn enia lati Beerṣeba de òke Efraimu, o si mu wọn pada sọdọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn. 5 O si fi awọn onidajọ si ilẹ na, ninu gbogbo ilu olodi Juda, lati ilu de ilu, 6 O si wi fun awọn onidajọ pe, Ẹ kiyesi ohun ti ẹnyin nṣe! nitori ti ẹnyin kò dajọ fun enia bikòṣe fun Oluwa, ti o wà pẹlu nyin ninu ọ̀ran idajọ. 7 Njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹ̀ru Oluwa ki o wà lara nyin, ẹ ma ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti kò si aiṣedede kan lọdọ Oluwa Ọlọrun wa, tabi ojuṣaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ. 8 Pẹlupẹlu ni Jerusalemu, Jehoṣafati yàn ninu awọn ọmọ Lefi, ati ninu awọn alufa, ati ninu awọn olori awọn baba Israeli, fun idajọ Oluwa, ati fun ẹjọ; nwọn si ngbe Jerusalemu. 9 O si kilọ fun wọn, wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o mã ṣe, ni ibẹ̀ru Oluwa, li otitọ, ati pẹlu ọkàn pipé. 10 Ẹjọ ki ẹjọ ti o ba si de ọdọ nyin lati ọdọ awọn arakunrin nyin ti ngbe ilu wọn, lãrin ẹ̀jẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ofin pẹlu aṣẹ, ìlana ati ẹtọ́, ki ẹnyin ki o kilọ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe dẹṣẹ si Oluwa, ibinu a si wá sori nyin, ati sori awọn arakunrin nyin: ẹ ṣe bẹ̃ gẹgẹ, ẹnyin kì yio si jẹbi. 11 Si wõ, Amariah, alufa ni olori lori nyin ni gbogbo ọ̀ran Oluwa; ati Sebadiah, ọmọ Iṣmaeli, alakoso ile Juda, fun ọ̀ran ọba; pẹlupẹlu ẹnyin ni olutọju awọn ọmọ Lefi pẹlu nyin. Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe, Oluwa yio pẹlu ẹni-rere.

2 Kronika 20

Wọ́n Gbógun ti Edomu

1 O SI ṣe, lẹhin eyi li awọn ọmọ Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni, ati ninu awọn ọmọ Edomu pẹlu wọn, gbé ogun tọ Jehoṣafati wá. 2 Nigbana li awọn kan wá, nwọn si wi fun Jehoṣafati pe, Ọ̀pọlọpọ enia mbo wá ba ọ lati apakeji okun lati Siria, si kiyesi i, nwọn wà ni Hasason-Tamari ti iṣe Engedi. 3 Jehoṣafati si bẹ̀ru, o si fi ara rẹ̀ si ati wá Oluwa, o si kede àwẹ ja gbogbo Juda. 4 Juda si kó ara wọn jọ, lati wá iranlọwọ lọwọ Oluwa: pẹlupẹlu nwọn wá lati inu gbogbo ilu Juda lati wá Oluwa, 5 Jehoṣafati si duro ninu apejọ enia Juda ati Jerusalemu, ni ile Oluwa, niwaju àgbala titun. 6 O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju? 7 Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai? 8 Nwọn si ngbe inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ibi-mimọ́ fun ọ ninu rẹ̀ fun orukọ rẹ, pe, 9 Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ. 10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, ati awọn ara òke Seiri, ti iwọ kò jẹ ki Israeli gbogun si nigbati nwọn jade ti ilẹ Egipti wá, ṣugbọn nwọn yipada kuro lọdọ wọn, nwọn kò si run wọn; 11 Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni. 12 Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ. 13 Gbogbo Juda si duro niwaju Oluwa, pẹlu awọn ọmọ wẹrẹ wọn, obinrin wọn, ati ọmọ wọn. 14 Ṣugbọn lori Jahasieli, ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah, ọmọ Lefi kan ninu awọn ọmọ Asafu, ni ẹmi Oluwa wá li ãrin apejọ enia na. 15 O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun. 16 Lọla sọ̀kalẹ tọ̀ wọn: kiyesi i, nwọn o gbà ibi igòke Sisi wá; ẹnyin o si ri wọn ni ipẹkun odò na, niwaju aginju Jerueli. 17 Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin. 18 Jehoṣafati tẹ ori rẹ̀ ba silẹ: ati gbogbo Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu wolẹ niwaju Oluwa lati sìn Oluwa. 19 Awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Kohati ati ninu awọn ọmọ Kori si dide duro, lati fi ohùn rara kọrin iyìn soke si Oluwa Ọlọrun Israeli. 20 Nwọn si dide ni kutukutu owurọ, nwọn si jade lọ si aginju Tekoa: bi nwọn si ti jade lọ, Jehoṣafati duro, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ará Juda, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu. Ẹ gbà Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́, bẹ̃li a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ̀ gbọ́, bẹ̃li ẹnyin o ṣe rere. 21 O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. 22 Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn. 23 Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji. 24 Nigbati Juda si de iha ile-iṣọ li aginju, nwọn wò awọn ọ̀pọlọpọ enia, si kiyesi i, okú ti o ṣubu lulẹ ni nwọn, ẹnikan kò sá asalà. 25 Nigbati Jehoṣafati ati awọn enia rẹ̀ de lati kó ikogun wọn, nwọn ri lara wọn ọ̀pọlọpọ ọrọ̀, ati okú, ati ohun-elo iyebiye, nwọn si kójọ fun ara wọn, jù eyiti nwọn le kó lọ: nwọn si kó ikogun wọn jọ ni ijọ mẹta, nitoriti o sa papọ̀ju. 26 Ati li ọjọ kẹrin nwọn kó ara wọn jọ li afonifoji Ibukún, nitori nibẹ ni nwọn fi ibukún fun Oluwa, nitorina ni a ṣe npe orukọ ibẹ na ni, Afonifoji Ibukún, titi di oni. 27 Nigbana ni nwọn yipada, gbogbo awọn ọkunrin Juda ati Jerusalemu, ati Jehoṣafati niwaju wọn lati pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀; nitori ti Oluwa ti mu wọn yọ̀ lori awọn ọta wọn. 28 Nwọn si wá si Jerusalemu pẹlu ohun-elo orin, ati duru ati ipè si ile Oluwa. 29 Ibẹ̀ru Ọlọrun si wà lara gbogbo ijọba ilẹ wọnni, nigbati nwọn gbọ́ pe Oluwa ti ba awọn ọta Israeli jà. 30 Bẹ̃ni ijọba Jehoṣafati wà li alafia: nitoriti Ọlọrun rẹ̀ fun u ni isimi yikakiri.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Jehoṣafati

31 Jehoṣafati si jọba lori Juda: o si wà li ẹni ọdun marundilogoji, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹdọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Asuba, ọmọbinrin Ṣilhi. 32 O si rìn li ọ̀na Asa, baba rẹ̀, kò si yà kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyi ti o tọ́ li oju Oluwa. 33 Sibẹ kò mu ibi giga wọnni kuro: pẹlupẹlu awọn enia na kò si fi ọkàn wọn fun Ọlọrun awọn baba wọn rara. 34 Ati iyokù iṣe Jehoṣafati, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyẹsi i, a kọ wọn sinu iwe Jehu, ọmọ Hanani, a si ti fi i sinu iwe awọn ọba Israeli. 35 Ati lẹhin eyi ni Jehoṣafati, ọba Juda, dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, ọba Israeli, ẹniti o ṣe buburu gidigidi: 36 O si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ ọ lati kan ọkọ̀ lati lọ si Tarṣiṣi: nwọn si kàn ọkọ̀ ni Esion-Geberi. 37 Nigbana ni Elieseri ọmọ Dodafah ti Mareṣa sọtẹlẹ si Jehoṣafati wipe, Nitori ti iwọ ti dá ara rẹ pọ̀ mọ Ahasiah, Oluwa ti ba iṣẹ rẹ jẹ. Awọn ọkọ̀ na si fọ́, nwọn kò si le lọ si Tarṣiṣi.

2 Kronika 21

1 JEHOṢAFATI si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Jehoramu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Jehoramu, Ọba Juda

2 O si ni awọn arakunrin, awọn ọmọ Jehoṣafati, Asariah, ati Jehieli, ati Sekariah, ati Asariah ati Mikaeli, ati Ṣefatiah: gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda. 3 Baba wọn si bun wọn li ẹ̀bun pupọ, ni fadakà ati ni wura, ati ohun iyebiye, pẹlu ilu olodi ni Juda, ṣugbọn o fi ijọba fun Jehoramu: nitori on li akọbi. 4 Nigbati Jehoramu si dide si ijọba baba rẹ̀, o mu ara rẹ̀ le, o si fi idà pa gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati ninu awọn ijoye Israeli. 5 Jehoramu jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọ̀n nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹjọ ni Jerusalemu. 6 O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, gẹgẹ bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o ni ọmọbinrin Ahabu li aya: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa. 7 Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa ile Dafidi run, nitori majẹmu ti o ti ba Dafidi da, ati bi o ti ṣe ileri lati fun u ni imọlẹ kan ati fun awọn ọmọ rẹ̀ lailai. 8 Li ọjọ rẹ̀ li awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn. 9 Nigbana ni Jehoramu rekọja lọ pẹlu awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o ká a mọ, ati awọn olori kẹkẹ́. 10 Sibẹ awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, titi di oni yi. Akokò na pẹlu ni Libna ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ rẹ̀; nitoriti o ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ. 11 Pẹlupẹlu o ṣe ibi giga wọnni lori òke Judah, o si mu ki awọn olugbe Jerusalemu ki o ṣe àgbere, o si mu Juda ṣẹ̀. 12 Iwe kan si ti ọdọ Elijah, woli, wá si ọdọ rẹ̀ wipe: Bayi li Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, nitoriti iwọ kò rìn li ọ̀na Jehoṣafati, baba rẹ, tabi li ọ̀na Asa, ọba Juda; 13 Ṣugbọn ti iwọ rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, iwọ si ti mu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu tọ ọ̀na panṣaga, gẹgẹ bi panṣaga ile Ahabu, ati ti iwọ si pa awọn arakunrin ile baba rẹ ti o jẹ ẹni-rere jù iwọ lọ: 14 Kiyesi i, Oluwa yio fi àjakalẹ-arun nla kọlù awọn enia rẹ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn obinrin rẹ, ati gbogbo ọrọ̀ rẹ: 15 Iwọ o ṣe aisan pupọ, àrun nla ninu ifun rẹ, titi ifun rẹ yio fi tu jade nitori àrun ọjọ pupọ. 16 Pẹlupẹlu, Oluwa ru ẹmi awọn ara Filistia, ati ti awọn ara Arabia, ti o sunmọ awọn ara Etiopia, soke si Jehoramu. 17 Nwọn si gòke wá si Juda, nwọn si ya wọle, nwọn si kó gbogbo ọrọ̀ ti a ri ni ile ọba ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, ati awọn obinrin rẹ̀, ni igbekun lọ; tobẹ̃ ti a kò ṣẹ́ku ọkunrin kan silẹ fun u, bikòṣe Jehoahasi, abikẹhin ninu awọn ọmọ rẹ̀. 18 Lẹhin gbogbo eyi Oluwa fi àrun, ti a kò le wòsan, kọlù u ni ifun. 19 O si ṣe bẹ̃ bi akokò ti nlọ ati lẹhin ọdun meji, ni ifun rẹ̀ tu jade nitori aìsan rẹ̀, o si kú ninu irora buburu na: awọn enia rẹ̀ kò si ṣe ijona fun u gẹgẹ bi ijona ti awọn baba rẹ̀. 20 Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu, o si fi ilẹ silẹ laiwu ni: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi; ṣugbọn kì iṣe ninu iboji awọn ọba.

2 Kronika 22

Ahasaya Ọba Juda

1 AWỌN olugbe Jerusalemu, si fi Ahasiah, ọmọ rẹ̀ abikẹhin, jọba ni ipò rẹ̀: nitori awọn ẹgbẹ́ ogun, ti o ba awọn ara Arabia wá ibudo, ti pa gbogbo awọn ẹgbọn. Bẹ̃ni Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, jọba. 2 Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Ataliah, ọmọbinrin Omri. 3 On pẹlu rìn li ọ̀na Ahabu: nitori iya rẹ̀ ni igbimọ̀ rẹ̀ lati ṣe buburu. 4 O si ṣe buburu loju Oluwa bi ile Ahabu: nitori awọn wọnyi li o nṣe igbimọ̀ rẹ̀ lẹhin ikú baba rẹ̀ si iparun rẹ̀. 5 O tẹle imọ̀ran wọn pẹlu; o si ba Jehoramu, ọmọ Ahabu, ọba Israeli, lọ iba Hasaeli, ọba Siria jagun, ni Ramoti-Gileadi: awọn ara Siria si ṣá Jehoramu li ọgbẹ. 6 O si pada lọ iwora ni Jesreeli, nitori ọgbẹ ti a ṣá a ni Rama, nigbati o fi ba Hasaeli, ọba Siria jà. Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, si sọ̀kalẹ lọ iwò Jehoramu, ọmọ Ahabu, ni Jesreeli, nitoriti o ṣaisan. 7 Iparun Ahasiah lati ọwọ Ọlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ̀ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro. 8 O si ṣe nigbati Jehu nmu idajọ ṣẹ sori ile Ahabu, o si ri awọn ijoye Juda, ati awọn ọmọ awọn arakunrin Ahasiah, ti nṣe iranṣẹ fun Ahasiah, o si pa wọn. 9 O si wá Ahasiah: nwọn si mu u, (on sa ti fi ara pamọ́ ni Samaria,) nwọn si mu u tọ̀ Jehu wá: nigbati nwọn si pa a tan, nwọn sìn i: nitori ti nwọn wipe, ọmọ Jehoṣafati ni, ẹniti o wá Oluwa tọkàntọkan rẹ̀. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ni ile Ahasiah ti o yẹ fun ijọba.

Atalaya, Ọbabinrin ní Juda

10 Ṣugbọn nigbati Ataliah, iya Ahasiah, ri pe ọmọ on kú, o dide o si run gbogbo iru ọmọ ijọba ile Judah. 11 Ṣugbọn Jehoṣabeati, ọmọbinrin ọba, mu Joaṣi, ọmọ Ahasiah, o ji i kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa, o fi on ati olutọ rẹ̀ sinu yẹwu Ibusùn. Bẹ̃ni Jehoṣabeati, ọmọbinrin Jehoramu ọba, aya Jehoiada, alufa, (nitori arabinrin Ahasiah li on) o pa a mọ́ kuro lọdọ Ataliah ki o má ba pa a. 12 O si wà pẹlu wọn ni pipamọ́ ninu ile Ọlọrun li ọdun mẹfa: Ataliah si jọba lori ilẹ na.

2 Kronika 23

Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Atalaya

1 ATI li ọdun keje, Jehoiada mu ọkàn le, o si ba awọn olori ọrọrún dá majẹmu pẹlu, ani Asariah, ọmọ Jerohamu ati Iṣmaeli, ọmọ Jehohanani, ati Asariah ọmọ Obedi, ati Maaseiah, ọmọ Adaiah, ati Eliṣafati ọmọ Sikri. 2 Nwọn si lọ kakiri ni Juda, nwọn si kó awọn ọmọ Lefi jọ lati inu gbogbo ilu Juda, ati olori awọn baba ni Israeli, nwọn si wá si Jerusalemu. 3 Gbogbo ijọ enia si ba ọba dá majẹmu ni ile Ọlọrun. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, ọmọ ọba ni yio jọba, gẹgẹ bi Oluwa ti wi niti awọn ọmọ Dafidi. 4 Eyi li ohun ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin yio wọle li ọjọ isimi, ninu awọn alufa ati ninu awọn ọmọ Lefi, ti yio ṣe adena iloro; 5 Idamẹta yio wà ni ile ọba: idamẹta yio si wà ni ẹnu-ọ̀na ti a npè ni ile Ipilẹ: ati gbogbo enia yio wà li àgbala ile Oluwa. 6 Ṣugbọn ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o wọ̀ ile Oluwa wá, bikoṣe awọn alufa, ati awọn ti nṣe iranṣẹ fun awọn ọmọ Lefi: nwọn o wọle, nitori mimọ́ ni nwọn: gbogbo awọn enia yio si ṣọ́ ẹṣọ́ Oluwa. 7 Awọn ọmọ Lefi yio yi ọba ka kakiri, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba wá si iha ile na, a o si pa a: ṣugbọn ki ẹnyin ki o wà pẹlu ọba, nigbati o ba nwọ̀ ile, ati nigbati o ba njade. 8 Bẹ̃li awọn ọmọ Lefi ati gbogbo Juda ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada, alufa ti pa á ni aṣẹ, olukuluku si mu awọn enia rẹ̀ ti o nwọle li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti o njade li ọjọ isimi nitori Jehoiada alufa, kò jọwọ awọn ẹgbẹ meji alufa lọwọ lọ. 9 Jehoiada alufa, si fi ọ̀kọ ati asà, ati apata wọnni ti iti ṣe ti Dafidi ọba, ti o ti wà ni ile Ọlọrun, fun awọn balogun ọrọrun. 10 O si tò gbogbo awọn enia tì ọba kakiri olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀, lati apa ọtún ile na titi de apa òsi ile na, lẹba pẹpẹ ati lẹba ile na. 11 Nigbana ni nwọn mu ọmọ ọba jade wá, nwọn si fi ade fun u ati iwe ẹri na, nwọn si fi i jọba: Jehoiada ati awọn ọmọ rẹ̀ si fi ororo yàn a, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ. 12 Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn enia, ti nwọn nsare lọ sibẹ, ti nwọn si nyìn ọba, o si tọ awọn enia na wá sinu ile Oluwa: 13 O si wò, si kiyesi i, ọba duro ni ibuduro rẹ̀ li ẹba ẹnu-ọ̀na, ati awọn balogun ati awọn afunpè lọdọ ọba: ati gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè, ati awọn akọrin pẹlu ohun-elo orin, ati awọn ti nkede lati kọ orin iyin. Nigbana ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe: Ọ̀tẹ! Ọ̀tẹ! 14 Nigbana ni Jehoiada alufa mu awọn olori ọrọrun ani awọn olori ogun na jade, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade kuro ninu ile sẹhin àgbala: ẹni-kẹni ti o ba si tọ̀ ọ lẹhin, ni ki a fi idà pa. Nitori alufa wipe, Ẹ máṣe pa a ninu ile Oluwa. 15 Nwọn si fi àye fun u; nigbati o si de atiwọ̀ ẹnu-ọ̀na Ẹṣin ile ọba, nwọn si pa a nibẹ.

Jehoiada Ṣe Àtúnṣe

16 Jehoiada dá majẹmu lãrin on ati lãrin awọn enia, ati lãrin ọba pe, enia Oluwa li awọn o ma ṣe. 17 Gbogbo awọn enia na si lọ si ile Baali, nwọn si wó o lulẹ, nwọn si fọ pẹpẹ ati awọn ere rẹ̀ tũtu, nwọn si pa Mattani alufa Baali, niwaju pẹpẹ. 18 Jehoiada si fi iṣẹ itọju ile Oluwa le ọwọ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ti Dafidi ti pin lori ile Oluwa, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, pẹlu ayọ̀ ati pẹlu orin lati ọwọ Dafidi. 19 O si fi awọn adena si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ki ẹni alaimọ́ ninu ohun-kohun ki o má ba wọ̀ ọ. 20 O si mu awọn olori-ọrọrun, ati awọn ọlọla, ati awọn bãlẹ ninu awọn enia ati gbogbo enia ilẹ na, nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá: nwọn si gbà ẹnu-ọ̀na giga wá sinu ile ọba, nwọn si gbé ọba ka ori itẹ ijọba na. 21 Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀: ilu na si tòro lẹhin ti a fi idà pa Ataliah.

2 Kronika 24

Joaṣi, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun meje ni Joaṣi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ogoji ọdun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Sibia ti Beer-ṣeba. 2 Joaṣi si ṣe eyiti o tọ li oju Oluwa ni gbogbo ọjọ Jehoiada, alufa. 3 Jehoiada si fẹ obinrin meji fun u, o si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin. 4 O si ṣe lẹhin eyi, o wà li ọkàn Joaṣi lati tun ile Oluwa ṣe. 5 O si kó awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi jọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, ki ẹ si gbà owo jọ lati ọwọ gbogbo Israeli, lati tun ile Ọlọrun nyin ṣe li ọdọdun, ki ẹ si mu ọ̀ran na yá kankan. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi kò mu ọ̀ran na yá kánkan. 6 Ọba si pè Jehoiada, olori, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ kò bère li ọwọ awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o mu owo ofin Mose, iranṣẹ Oluwa, lati Juda ati lati Jerusalemu wá, ati ti ijọ-enia Israeli fun agọ ẹri? 7 Nitori Ataliah, obinrin buburu nì ati awọn ọmọ rẹ ti fọ ile Ọlọrun; ati pẹlu gbogbo ohun mimọ́ ile Oluwa ni nwọn fi ṣe ìsin fun Baalimu. 8 Ọba si paṣẹ, nwọn si kàn apoti kan, nwọn si fi si ita li ẹnu-ọ̀na ile Oluwa. 9 Nwọn si kede ni Juda ati Jerusalemu, lati mu owo ofin fun Oluwa wá, ti Mose iranṣẹ Ọlọrun, fi le Israeli lori li aginju. 10 Gbogbo awọn ijoye ati gbogbo awọn enia si yọ̀, nwọn si mu wá, nwọn fi sinu apoti na, titi o fi kún. 11 O si ṣe, nigbati akokò de lati mu apoti na wá sọdọ olutọju iṣẹ ọba nipa ọwọ awọn ọmọ Lefi, nigbati nwọn si ri pe, owo pọ̀, akọwe ọba ati olori ninu awọn alufa a wá, nwọn a si dà apoti na, nwọn a mu u, nwọn a si tun mu u pada lọ si ipò rẹ̀. Bayi ni nwọn nṣe li ojojumọ, nwọn si kó owo jọ li ọ̀pọlọpọ. 12 Ati ọba ati Jehoiada fi i fun iru awọn ti nṣiṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi gbà àgbaṣe awọn oniṣọ̀nà okuta, ati awọn gbẹnàgbẹna, lati tun ile Oluwa ṣe, ati pẹlu awọn alagbẹdẹ irin, ati idẹ, lati tun ile Oluwa ṣe. 13 Bẹ̃li awọn ti o nṣiṣẹ ṣiṣẹ na, iṣẹ na si lọ siwaju ati siwaju li ọwọ wọn, nwọn si tun mu ile Ọlọrun duro si ipò rẹ̀, nwọn si mu u le. 14 Nigbati nwọn si pari rẹ̀ tan, nwọn mu owo iyokù wá si iwaju ọba ati Jehoiada, a si fi i ṣe ohun-elo fun ile Oluwa, ani ohun-elo fun ìsin ati fun ẹbọ, pẹlu ọpọ́n, ani ohun-elo wura ati fadakà. Nwọn si ru ẹbọ sisun ni ile Oluwa nigba-gbogbo ni gbogbo ọjọ Jehoiada.

Wọ́n Yí Ètò ìjọba Jehoiada pada

15 Ṣugbọn Jehoiada di arugbo, o si kún fun ọjọ, o si kú, ẹni ãdoje ọdun ni nigbati o kú. 16 Nwọn si sìn i ni ilu Dafidi pẹlu awọn ọba, nitoriti o ṣe rere ni Israeli, ati si Ọlọrun, ati si ile rẹ̀. 17 Lẹhin ikú Jehoiada awọn ijoye Juda de, nwọn si tẹriba fun ọba. Nigbana li ọba si gbọ́ ti wọn. 18 Nwọn si kọ̀ ile Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, nwọn si nsìn òriṣa ati ere: ibinu si wá sori Juda ati Jerusalemu nitori ẹ̀ṣẹ wọn yi. 19 Sibẹ o rán awọn woli si wọn, lati mu wọn pada tọ̀ Oluwa wá; nwọn si jẹri gbè wọn; ṣugbọn nwọn kò fi eti si i. 20 Ẹmi Ọlọrun si bà le Sakariah, ọmọ Jehoiada alufa, ti o duro ni ibi giga jù awọn enia lọ, o si wi fun wọn pe, Bayi li Ọlọrun wi pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin Oluwa, ẹnyin kì yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ̀ Oluwa silẹ, on pẹlu si ti kọ̀ nyin. 21 Nwọn si di rikiṣi si i, nwọn si sọ ọ li okuta nipa aṣẹ ọba li agbala ile Oluwa. 22 Bẹ̃ni Joaṣi, ọba, kò ranti õre ti Jehoiada, baba rẹ̀, ti ṣe fun u, o si pa ọmọ rẹ̀. Nigbati o si nkú lọ, o wipe, Ki Oluwa ki o wò o, ki o si bère rẹ̀.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Joaṣi

23 O si ṣe li opin ọdun ni ogun Siria gòke tọ̀ ọ wá: nwọn si de Juda ati Jerusalemu, nwọn si pa gbogbo awọn ijoye enia run kuro ninu awọn enia na, nwọn si rán gbogbo ikógun wọn sọdọ ọba Damasku. 24 Nitori ogun awọn ara Siria dé pẹlu ẹgbẹ diẹ, Oluwa si fi ogun ti o pọ̀ gidigidi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ. Bẹ̃ni nwọn si ṣe idajọ Joaṣi. 25 Nigbati nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, (nwọn sa ti fi i silẹ ninu àrun nla) awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nitori ẹ̀jẹ awọn ọmọ Jehoiada alufa, nwọn si pa a lori akete rẹ̀, o si kú: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi, ṣugbọn nwọn kò sìn i ni iboji awọn ọba. 26 Wọnyi li awọn ti o di rikiṣi si i, Sabadi, ọmọ Simeati, obinrin ara Ammoni, ati Jehosabadi, ọmọ Ṣimriti, obinrin ara Moabu. 27 Njẹ niti awọn ọmọ rẹ̀, ati titobi owo-ọba, ti a fi le e lori, ati atunṣe ile Ọlọrun, kiyesi i, a kọ wọn sinu itan iwe awọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 25

Amasaya, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Amasiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jehoaddani ti Jerusalemu. 2 O si ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe pẹlu ọkàn pipé. 3 O si ṣe, nigbati a fi idi ijọba na mulẹ fun u, o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o pa ọba, baba rẹ̀, 4 Ṣugbọn kò pa awọn ọmọ wọn, ṣugbọn o ṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin ninu iwe Mose, ti Oluwa ti paṣẹ wipe, Awọn baba kì yio kú fun awọn ọmọ, bẹ̃li awọn ọmọ kì yio kú fun awọn baba, ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

Wọ́n Gbógun ti Edomu

5 Amasiah si kó Juda jọ, o si tò wọn lẹsẹsẹ gẹgẹ bi ile baba wọn, awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati balogun ọrọrun, ani gbogbo Juda ati Benjamini, o si ka iye wọn lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̀ lọ, o si ri wọn li ọkẹ mẹdogun enia ti a yàn, ti o le jade lọ si ogun, ti o si le lo ọ̀kọ ati asà. 6 O si bẹ̀ ọkẹ marun ogun alagbara akọni ọkunrin lati inu Israeli wá fun ọgọrun talenti fadakà. 7 Ṣugbọn enia Ọlọrun kan tọ̀ ọ wá, wipe, Ọba, máṣe jẹ ki ogun Israeli ki o ba ọ lọ: nitoriti Oluwa kò wà pẹlu Israeli, ani gbogbo awọn ọmọ Efraimu. 8 Ṣugbọn bi iwọ o ba lọ, ma lọ, mu ara le fun ogun na: Ọlọrun yio bì ọ ṣubu niwaju ọta: Ọlọrun sa li agbara lati ṣe iranlọwọ, ati lati bì ni ṣubu. 9 Amasiah si wi fun enia Ọlọrun na pe, Ṣugbọn kili awa o ha ṣe nitori ọgọrun talenti ti mo ti fi fun ẹgbẹ-ogun Israeli? Enia Ọlọrun na si dahùn pe, O wà li ọwọ Oluwa lati fun ọ li ọ̀pọlọpọ jù eyi lọ. 10 Nigbana li Amasiah yà wọn, ani ẹgbẹ-ogun ti o ti tọ̀ ọ lati Efraimu wá, lati tun pada lọ ile wọn: ibinu wọn si ru gidigidi si Juda, nwọn si pada si ile wọn ni irunu. 11 Amasiah si mu ara le, o si kó awọn enia rẹ̀ jade, o si lọ si afonifoji iyọ̀, o si pa ẹgbarun ninu awọn ọmọ Seiri. 12 Ati ẹgbãrun alãye li awọn ọmọ Juda kó ni igbekun lọ, nwọn si mu wọn lọ si òke apata na, nwọn si tãri wọn silẹ lati òke apata na, nwọn si fọ́ tũtu. 13 Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun ti Amasiah ran pada lọ, ki nwọn ki o máṣe ba on lọ si ogun, kọlù awọn ilu Juda lati Samaria titi de Bet-horoni, nwọn si pa ẹgbẹdogun ninu wọn, nwọn si kó ikógun pipọ. 14 O si ṣe lẹhin ti Amasiah ti ibi pipa awọn ara Edomu bọ̀, o si mu awọn oriṣa awọn ọmọ Seiri bọ̀, o si gà wọn li oriṣa fun ara rẹ̀, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba niwaju wọn, o si sun turari fun wọn. 15 Nitorina ni ibinu Oluwa ru si Amasiah, o si ran woli kan si i, ti o wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nwá oriṣa awọn enia na, ti kò le gbà awọn enia wọn lọwọ rẹ? 16 O si ṣe bi o ti mba a sọ̀rọ, ọba si wi fun u pe, A ha fi ọ ṣe igbimọ̀ ọba bi? fi mọ: ẹ̃ṣe ti a o fi pa ọ? Nigbana ni woli na fi mọ; o si wipe, Emi mọ̀ pe, Ọlọrun ti pinnu rẹ̀ lati pa ọ run, nitoriti iwọ ti ṣe eyi, ti iwọ kò si tẹ eti si imọ̀ran mi.

Amasaya Gbógun ti Israẹli

17 Nigbana ni Amasiah, ọba Juda, gbà ẹ̀kọ, o si ranṣẹ si Joaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu ọba Israeli, wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju. 18 Joaṣi, ọba Israeli, si ranṣẹ si Amasiah, ọba Judah, wipe, Ẹgun-ọ̀gan ti o wà ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti o wà ni Lebanoni, wipe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ mi li aya: ẹranko igbẹ kan ti o wà ni Lebanoni si kọja nibẹ, o si tẹ ẹ̀gun-ọ̀gan na mọlẹ. 19 Iwọ wipe, Kiyesi i, iwọ ti pa awọn ara Edomu; ọkàn rẹ si gbé soke lati ma ṣogo: njẹ gbe ile rẹ, ẽṣe ti iwọ nfiran fun ifarapa rẹ, ti iwọ o fi ṣubu, ani iwọ ati Juda pẹlu rẹ? 20 Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́; nitori lati ọdọ Ọlọrun wá ni, ki o le fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ, nitoriti nwọn nwá awọn oriṣa Edomu. 21 Bẹ̃ni Joaṣi, ọba Israeli gòke lọ; nwọn si wò ara wọn li oju, on ati Amasiah, ọba Juda, ni Bet-Ṣemeṣi ti iṣe ti Juda, 22 A si ṣẹ́ Juda niwaju Israeli, nwọn salọ olukuluku sinu agọ rẹ̀. 23 Joaṣi ọba Israeli si mu Amasiah, ọba Juda ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasiah ni Bet-Ṣemeṣi, o si mu u wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu lati ẹnubode Efraimu titi de ẹnu-bode igun, irinwo igbọnwọ. 24 O si mu gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun-elo ti a ri ni ile Ọlọrun lọdọ Obed-Edomu, ati awọn iṣura ile ọba, ati awọn ògo pẹlu, o si pada lọ si Samaria. 25 Amasiah, ọmọ Joaṣi, ọba Juda, wà li ãye lẹhin ikú Joaṣi, ọmọ Jehoahasi ọba Israeli, li ọdun mẹdogun. 26 Ati iyokù iṣe Amasiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kò ha kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli? 27 Njẹ lẹhin àkoko ti Amasiah yipada kuro lati ma tọ̀ Oluwa lẹhin, nwọn di ọ̀tẹ si i ni Jerusalemu; o si salọ si Lakiṣi: ṣugbọn nwọn ranṣẹ tẹlẽ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ. 28 Nwọn si mu u wá lori ẹṣin, nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.

2 Kronika 26

Usaya, Ọba Juda

1 NIGBANA ni gbogbo enia Juda mu Ussiah ti iṣe ẹni ọdun mẹrindilogun, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀, Amasiah. 2 On kọ́ Elotu, o si mu u pada fun Juda; lẹhin ti ọba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀. 3 Ẹni ọdun mẹrindilogun ni Ussiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jekoliah ti Jerusalemu. 4 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀, Amasiah, ti ṣe. 5 O si wá Ọlọrun li ọjọ Sekariah, ẹniti o li oye ninu iran Ọlọrun: niwọn ọjọ ti o wá Oluwa, Ọlọrun si mu u ṣe rere. 6 O si jade lọ, o si ba awọn ara Filistia jagun, o si wó odi Gati ati odi Jabne ati odi Aṣdodu, o si kọ́ ilu wọnni ni Aṣdodu, ati lãrin awọn ara Filistia. 7 Ọlọrun si ràn a lọwọ si awọn ara Filistia, ati si awọn ara Arabia, ti ngbe ni Gur-Baali, ati awọn ara Mehuni. 8 Awọn ara Ammoni ta Ussiah li ọrẹ: orukọ rẹ̀ si tàn lọ kakiri titi de atiwọ Egipti; nitoriti o mu ara rẹ̀ le gidigidi. 9 Ussiah si kọ́ ile iṣọ ni Jerusalemu, nibi ẹnu-bode Igun, ati nibi ẹnu-bode Afonifoji, ati nibi iṣẹpo-odi, o si mu wọn le. 10 O kọ́ ile iṣọ li aginju pẹlu, o si wà kanga pupọ: nitoriti o li ẹran-ọsin pipọ, ati ni ilẹ isalẹ, ati ni pẹ̀tẹlẹ: o ni àgbẹ ati awọn olutọju àjara lori òke nla, ati lori Karmeli: nitoriti o fẹran àgbẹ-ṣiṣe. 11 Ussiah si li ẹgbẹ́-ogun awọn enia ti njagun, ti ima lọ ijagun li ẹgbẹgbẹ gẹgẹ bi iye kikà wọn, nipa ọwọ Jegieli, akọwe, ati Maaseiah, olori labẹ ọwọ Hananiah, ọkan ninu awọn olori ogun ọba. 12 Gbogbo iye olori awọn baba, alagbara akọni ogun jẹ ẹgbẹtala. 13 Ati li ọwọ wọn li agbara ogun kan wà, ọkẹ mẹdogun enia o le ẹ̃dẹgbãrin ti o mura, ti nfi àgbara nla jagun, lati ràn ọba lọwọ si ọta. 14 Ussiah si pesè fun wọn, já gbogbo ogun na, asà ati ọ̀kọ, ati akoro, ati ohun ihamọra-ọrùn, ati ọrun titi de okuta kànakàna. 15 O si ṣe ohun ẹrọ-ijagun ni Jerusalemu, ihumọ ọlọgbọ́n enia, lati wà lori ile-iṣọ, ati lori igun odi, lati fi tafa, ati lati fi sọ okuta nla. Orukọ rẹ̀ si tàn lọ jìnajina, nitoriti a ṣe iranlọwọ iyanu fun u, titi o fi li agbara.

Usaya Jìyà nítorí Ìwà Ìgbéraga Rẹ̀

16 Ṣugbọn nigbati o li agbara tan, ọkàn rẹ̀ gbé ga soke si iparun; nitoriti o ṣe irekọja si Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si lọ sinu tempili Oluwa, lati sun turari lori pẹpẹ turari. 17 Asariah, alufa si wọle tọ̀ ọ lọ ati ọgọrin alufa Oluwa pẹlu rẹ̀, awọn alagbara, 18 Nwọn si tako Ussiah ọba, nwọn si wi fun u pe, Ki iṣe tirẹ, Ussiah, lati sun turari fun Oluwa, bikòṣe ti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ti a yà si mimọ́ lati sun turari: jade kuro ni ibi mimọ́; nitoriti iwọ ti dẹṣẹ; bẹ̃ni kì yio ṣe fun ọlá rẹ lati ọdọ Oluwa Ọlọrun. 19 Nigbana ni Ussiah binu, awo-turari si mbẹ lọwọ rẹ̀ lati sun turari: ati nigbati o binu si awọn alufa, ẹ̀tẹ yọ ni iwaju rẹ̀, loju awọn alufa ni ile Oluwa lẹba pẹpẹ turari. 20 Ati Asariah, olori alufa, ati gbogbo awọn alufa wò o, si kiyesi i, o dẹtẹ ni iwaju rẹ̀, nwọn si tì i jade kuro nibẹ, nitõtọ, on tikararẹ̀ yara pẹlu lati jade, nitoriti Oluwa ti lù u. 21 Ussiah ọba, si di adẹ̀tẹ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile àrun, nitori adẹtẹ ni iṣe, nitoriti a ké e kuro ninu ile Oluwa: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si wà lori ile ọba, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na, 22 Ati iyokù iṣe Ussiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin ni Isaiah woli, ọmọ Amosi, kọ. 23 Bẹ̃ni Ussiah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni oko ìsinkú ti iṣe ti awọn ọba; nitoriti nwọn wipe, Adẹtẹ li on: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 27

Jotamu, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jotamu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku. 2 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe; kiki kò wọ inu tempili Oluwa lọ, ṣugbọn awọn enia nṣe ibi sibẹsibẹ. 3 On si kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa, ati lori odi Ofeli, o kọ́ pupọ. 4 Ani o kọ́ ilu wọnni li òke Juda, ati ninu igbo, o mọ ile-odi ati ile-iṣọ. 5 O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta. 6 Bẹ̃ni Jotamu di alagbara, nitoriti o tun ọ̀na rẹ̀ ṣe niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀. 7 Ati iyokù iṣe Jotamu ati gbogbo ogun rẹ̀, ati ọ̀na rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda. 8 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. 9 Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Ahasi, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 28

Ahasi, Ọba Juda

1 ẸNI ogun ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu: on kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀: 2 Nitoriti o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, o si ṣe ere didà fun Baalimu pẹlu. 3 O si sun turari li àfonifoji ọmọ Hinnomu, o si sun awọn ọmọ rẹ̀ ninu iná bi ohun-irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli. 4 O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori òke kekere, ati labẹ gbogbo igi tutu.

Ogun láàrin Siria ati Israẹli

5 Nitorina Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fi i le ọba Siria lọwọ; nwọn si kọlù u, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ni igbekun lọ ninu wọn, nwọn si mu wọn wá si Damasku. A si fi i le ọba Israeli lọwọ pẹlu, ti o pa a ni ipakupa. 6 Nitoriti Peka, ọmọ Remaliah, pa ọkẹ mẹfa enia ni Juda ni ijọ kan, gbogbo awọn ọmọ-ogun: nitoriti nwọn ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ. 7 Ati Sikri, alagbara kan ni Efraimu, pa Maaseiah, ọmọ ọba, ati Asirkamu, olori ile, ati Elkana, ibikeji ọba. 8 Awọn ọmọ Israeli si kó ọkẹ mẹwa ninu awọn arakunrin wọn ni igbekun lọ, awọn obinrin, awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin, nwọn si kó ikogun pupọ lọdọ wọn pẹlu, nwọn si mu ikogun na wá si Samaria.

Wolii Odedi

9 Woli Oluwa kan si wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Odedi: o si jade lọ ipade ogun ti o wá si Samaria, o si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nitoriti Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin binu si Juda li on ṣe fi wọn le nyin lọwọ, ẹnyin si pa wọn ni ipa-oro ti o de òke ọrun. 10 Ati nisisiyi ẹnyin npete lati tẹ awọn ọmọ Juda ati Jerusalemu ba fun ẹrú-kunrin ati ẹrú-birin nyin: ẹnyin kò ha jẹbi Oluwa Ọlọrun nyin, ani ẹnyin? 11 Njẹ nitorina, ẹ gbọ́ temi, ki ẹ si jọwọ awọn igbekun ti ẹnyin ti kó ni igbekun ninu awọn arakunrin nyin lọwọ lọ: nitori ibinu kikan Oluwa mbẹ lori nyin. 12 Nigbana li awọn kan ninu awọn olori, awọn ọmọ Efraimu, Asariah, ọmọ Johanani, Berekiah, ọmọ Meṣillemoti, ati Jehiskiah, ọmọ Ṣallumu, ati Amasa, ọmọ Hadlai, dide si awọn ti o ti ogun na bọ̀. 13 Nwọn si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ mu awọn igbekun nì wá ihin: nitori wò o, awa ti jẹbi niwaju Oluwa, ẹnyin npete ati fi kún ẹ̀ṣẹ ati ẹbi wa: ẹbi wa sa tobi, ibinu kikan si wà lori Israeli. 14 Bẹ̃li awọn enia ti o hamọra fi awọn igbekun ati ikogun na silẹ niwaju awọn ijoye, ati gbogbo ijọ enia. 15 Awọn ọkunrin ti a pè li orukọ na si dide, nwọn si mu awọn igbekun na, nwọn si fi ikogun na wọ̀ gbogbo awọn ti o wà ni ihoho ninu wọn, nwọn si wọ̀ wọn laṣọ, nwọn si bọ̀ wọn ni bàta, nwọn si fun wọn ni ohun jijẹ ati ohun mimu, nwọn si fi ororo kùn wọn li ara, nwọn si kó gbogbo awọn alailera ninu wọn sori kẹtẹkẹtẹ, nwọn si mu wọn wá si Jeriko, ilu ọlọpẹ si ọdọ arakunrin wọn: nigbana ni nwọn pada wá si Samaria.

Ahasi bẹ Asiria lọ́wẹ̀

16 Li akokò na ni Ahasi ọba, ranṣẹ si awọn ọba Assiria lati ràn on lọwọ. 17 Awọn ara Edomu si tun wá, nwọn si kọlù Juda, nwọn si kó igbekun diẹ lọ. 18 Awọn ara Filistia pẹlu ti gbé ogun lọ si ilu pẹtẹlẹ wọnni, ati siha gusu Juda, nwọn si ti gbà Bet-ṣemeṣi, ati Ajaloni, ati Gederoti, ati Ṣoko pẹlu ileto rẹ̀, Timna pẹlu ileto rẹ̀, ati Gimso pẹlu ati ileto rẹ̀: nwọn si ngbe ibẹ. 19 Nitoriti Oluwa ti rẹ̀ Juda silẹ nitori Ahasi, ọba Juda: nitoriti o mu Juda di alaini iranlọwọ, o si ṣe irekọja gidigidi si Oluwa. 20 Tilgati-pilnesari, ọba Assiria, si tọ̀ ọ wá, ọ si pọn ọ loju, ṣugbọn kò fun u li agbara. 21 Ahasi sa kó ninu ini ile Oluwa, ati ninu ile ọba, ati ti awọn ijoye, o si fi fun ọba Assiria: ṣugbọn kò ràn a lọwọ.

Ẹ̀ṣẹ̀ Ahasi

22 Ati li akokò ipọnju rẹ̀, o tun ṣe irekọja si i si Oluwa. Eyi ni Ahasi, ọba. 23 Nitori ti o rubọ si awọn oriṣa Damasku, awọn ẹniti o kọlù u: o si wipe, Nitoriti awọn oriṣa awọn ọba Siria ràn wọn lọwọ, nitorina li emi o rubọ si wọn, ki nwọn le ràn mi lọwọ. Ṣugbọn awọn na ni iparun rẹ̀ ati ti gbogbo Israeli. 24 Ahasi si kó gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun jọ, o si ké kuro lara ohun-elo ile Ọlọrun, o si tì ilẹkun ile Oluwa, o si tẹ́ pẹpẹ fun ara rẹ̀ ni gbogbo igun Jerusalemu. 25 Ati ni gbogbo orori ilu Juda li o ṣe ibi giga wọnni, lati sun turari fun awọn ọlọrun miran, o si mu Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀ binu. 26 Ati iyokù iṣe rẹ̀, ati ti gbogbo ọ̀na rẹ̀ ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli. 27 Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu na, ani ni Jerusalemu; ṣugbọn nwọn kò mu u wá sinu awọn isa-okú awọn ọba Israeli: Hesekiah ọmọ rẹ si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 29

Hesekaya, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Hesekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba fun ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Abijah, ọmọbinrin Sekariah. 2 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi, baba rẹ̀, ti ṣe.

Yíya Tẹmpili sí Mímọ́

3 Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li oṣù kini, o ṣí ilẹkun ile Oluwa, o si tun wọn ṣe. 4 O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi, o si kó wọn jọ si ita ila-õrun. 5 O si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ́ nisisiyi, ki ẹ si yà ile Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ́, ki ẹ si kó ohun aimọ́ na jade kuro ni ibi mimọ́. 6 Awọn baba wa sa ti dẹṣẹ, nwọn si ti ṣe ibi li oju Oluwa Ọlọrun wa, nwọn si ti kọ̀ ọ silẹ, nwọn si ti yi oju wọn pada kuro ni ibugbe Oluwa, nwọn si ti pa ẹhin wọn da. 7 Nwọn ti tì ilẹkun iloro na pẹlu, nwọn si ti pa fitila, nwọn kò si sun turari, bẹ̃ni nwọn kò ru ẹbọ sisun ni ibi mimọ́ si Ọlọrun Israeli. 8 Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri. 9 Sa wò o, awọn baba wa ti ti ipa idà ṣubu, ati awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, ati awọn obinrin wa wà ni igbekun nitori eyi. 10 Njẹ o wà li ọkàn mi lati ba Oluwa Ọlọrun Israeli dá majẹmu, ki ibinu rẹ̀ kikan ki o le yipada kuro lọdọ wa. 11 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari. 12 Nigbana li awọn ọmọ Lefi dide, Mahati, ọmọ Amasai, ati Joeli, ọmọ Asariah, ninu awọn ọmọ Kohati: ati ninu awọn ọmọ Merari, Kiṣi, ọmọ Abdi, ati Asariah, ọmọ Jehaleeli: ati ninu awọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma, ati Edeni, ọmọ Joah: 13 Ati ninu awọn ọmọ Elisafani, Ṣimri ati Jegieli: ati ninu awọn ọmọ Asafu, Sekariah ati Mattaniah. 14 Ati ninu awọn ọmọ Hemani, Jehieli ati Ṣimei: ati ninu awọn ọmọ Jedutuni, Ṣemaiah ati Ussieli. 15 Nwọn si kó awọn arakunrin wọn jọ, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si wá nipa aṣẹ ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, lati gbá ile Oluwa mọ́. 16 Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni. 17 Njẹ nwọn bẹ̀rẹ li ọjọ kini oṣù kini, lati yà a si mimọ́, ati li ọjọ kẹjọ oṣù na, nwọn de iloro Oluwa: bẹ̃ni nwọn fi ọjọ mẹjọ yà ile Oluwa si mimọ́; ati li ọjọ kẹrindilogun oṣù kini na, nwọn pari rẹ̀.

A Tún Tẹmpili Yà sí Mímọ́

18 Nigbana ni nwọn wọle tọ̀ Hesekiah ọba, nwọn si wipe: Awa ti gbá ile Oluwa mọ́, ati pẹpẹ ẹbọ sisun, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀, ati tabili akara-ifihan, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀. 19 Pẹlupẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ́ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, li akokò ijọba rẹ̀, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ́, si kiyesi i, nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ Oluwa. 20 Nigbana ni Hesekiah, ọba, dide ni kutukutu; o si kó awọn olori ilu jọ, o si gòke lọ sinu ile Oluwa. 21 Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa. 22 Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ. 23 Nwọn si mu awọn òbukọ ẹbọ-ẹ̀ṣẹ wá siwaju ọba ati ijọ enia na: nwọn si fi ọwọ wọn le wọn lori. 24 Awọn alufa si pa wọn, nwọn si fi ẹ̀jẹ wọn ṣe ilaja lori pẹpẹ, lati ṣe etutu fun gbogbo Israeli; nitoriti ọba paṣẹ, ki a ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli. 25 O si mu awọn ọmọ Lefi duro ninu ile Oluwa, pẹlu kimbali, pẹlu ohun-elo orin, ati pẹlu duru, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi, ati ti Gadi, ariran ọba, ati Natani, woli, nitori aṣẹ Oluwa ni lati ọwọ awọn woli rẹ̀. 26 Awọn ọmọ Lefi si duro pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ati awọn alufa pẹlu ipè. 27 Hesekiah si paṣẹ lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. Nigbati ẹbọ sisun na si bẹ̀rẹ, orin Oluwa bẹ̀rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israeli. 28 Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bẹ̃ titi ẹbọ sisun na fi pari tan. 29 Nigbati nwọn si ṣe ipari ẹbọ riru, ọba ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ tẹ̀ ara wọn ba, nwọn si sìn. 30 Pẹlupẹlu Hesekiah ọba, ati awọn ijoye paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, lati fi ọ̀rọ Dafidi ati ti Asafu ariran, kọrin iyìn si Oluwa: nwọn si fi inu-didùn kọrin iyìn, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sìn. 31 Nigbana ni Hesekiah dahùn, o si wipe, Nisisiyi, ọwọ nyin kún fun ẹ̀bun fun Oluwa, ẹ ṣunmọ ihin, ki ẹ si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá sinu ile Oluwa. Ijọ ẹnia si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá; ati olukuluku ti ọkàn rẹ̀ fẹ, mu ẹbọ sisun wá. 32 Iye ẹbọ sisun, ti ijọ enia mu wá, si jẹ ãdọrin akọ-malu, ati ọgọrun àgbo, ati igba ọdọ-agutan: gbogbo wọnyi si ni fun ẹbọ-sisun si Oluwa. 33 Awọn ohun ìyasi-mimọ́ si jẹ ẹgbẹta malu, ati ẹgbẹdogun agutan. 34 Ṣugbọn awọn alufa kò to, nwọn kò si le họ gbogbo awọn ẹran ẹbọ sisun na: nitorina awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi ràn wọn lọwọ, titi iṣẹ na fi pari, ati titi awọn alufa iyokù fi yà ara wọn si mimọ́: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ́. 35 Ati pẹlu, awọn ẹbọ sisun papọju, pẹlu ọra ẹbọ-alafia, pẹlu ẹbọ ohun-mimu fun ẹbọ sisun. Bẹ̃li a si to iṣẹ́-ìsin ile Oluwa li ẹsẹsẹ. 36 Hesekiah si yọ̀, ati gbogbo enia pe, Ọlọrun ti mura awọn enia na silẹ: nitori li ojiji li a ṣe nkan na.

2 Kronika 30

Ìmúra fún Àjọ Ìrékọjá

1 HESEKIAH si ranṣẹ si gbogbo Israeli ati Juda, o si kọ iwe pẹlu si Efraimu ati Manasse, ki nwọn ki o wá sinu ile Oluwa ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa, Ọlọrun Israeli. 2 Nitoriti ọba ti gbìmọ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ijọ-enia ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ li oṣù keji. 3 Nitoriti nwọn kò le pa a mọ́ li akokò na, nitori awọn alufa kò ti iyà ara wọn si mimọ́ to; bẹ̃li awọn enia kò ti ikó ara wọn jọ si Jerusalemu. 4 Ọran na si tọ́ loju ọba ati loju gbogbo ijọ-enia. 5 Bẹ̃ni nwọn fi aṣẹ kan lelẹ, lati kede ká gbogbo Israeli, lati Beer-ṣeba ani titi de Dani, lati wá ipa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa Ọlọrun Israeli ni Jerusalemu: nitori nwọn kò pa a mọ́ li ọjọ pupọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ. 6 Bẹ̃li awọn onṣẹ ti nsare lọ pẹlu iwe lati ọwọ ọba ati awọn ijoye rẹ̀ si gbogbo Israeli ati Juda; ati gẹgẹ bi aṣẹ ọba, wipe, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ tun yipada si Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, On o si yipada si awọn iyokù ninu nyin, ti o sala kuro lọwọ awọn ọba Assiria. 7 Ki ẹnyin ki o má si ṣe dabi awọn baba nyin, ati bi awọn arakunrin nyin, ti o dẹṣẹ si Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, nitorina li o ṣe fi wọn fun idahoro, bi ẹnyin ti ri. 8 Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọlọrùn lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Oluwa, ki ẹ si wọ̀ inu ibi-mimọ́ rẹ̀ lọ, ti on ti yà si mimọ́ titi lai: ki ẹ si sin Oluwa, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rẹ̀ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin. 9 Nitori bi ẹnyin ba tun yipada si Oluwa, awọn arakunrin nyin, ati awọn ọmọ nyin, yio ri ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni ìgbekun lọ, ki nwọn ki o le tun pada wá si ilẹ yi: nitori Oluwa Ọlọrun nyin, oniyọ́nu ati alãnu ni, kì yio si yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rẹ̀. 10 Bẹ̃ li awọn onṣẹ na kọja lati ilu de ilu, ni ilẹ Efraimu ati Manasse titi de Sebuluni: ṣugbọn nwọn fi wọn rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wọn. 11 Sibẹ omiran ninu awọn enia Aṣeri ati Manasse ati Sebuluni rẹ̀ ara wọn silẹ, nwọn si wá si Jerusalemu. 12 Ni Judah pẹlu, ọwọ Ọlọrun wà lati fun wọn li ọkàn kan lati pa ofin ọba mọ́ ati ti awọn ijoye, nipa ọ̀rọ Oluwa.

Àsè Àjọ Ìrékọjá

13 Ọ̀pọlọpọ enia si pejọ ni Jerusalemu, lati pa ajọ akara alaiwu mọ́ li oṣu keji, ijọ enia nlanla. 14 Nwọn si dide, nwọn si kó gbogbo pẹpẹ ti o wà ni Jerusalemu lọ, ati gbogbo pẹpẹ turari ni nwọn kó lọ, nwọn si dà wọn si odò Kidroni. 15 Nigbana ni nwọn pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù keji: oju si tì awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si mu ẹbọ sisun wá sinu ile Oluwa. 16 Nwọn si duro ni ipò wọn, bi ètò wọn gẹgẹ bi ofin Mose, enia Ọlọrun: awọn alufa wọ́n ẹ̀jẹ na, ti nwọn gbà lọwọ awọn ọmọ Lefi. 17 Nitori ọ̀pọlọpọ li o wà ninu ijọ enia na ti kò yà ara wọn si mimọ́: nitorina ni awọn ọmọ Lefi ṣe ntọju ati pa ẹran irekọja fun olukuluku ẹniti o ṣe alaimọ́, lati yà a si mimọ́ si Oluwa. 18 Ọ̀pọlọpọ enia, ani ọ̀pọlọpọ ninu Efraimu ati Manasse, Issakari, ati Sebuluni kò sa wẹ̀ ara wọn mọ́ sibẹ nwọn jẹ irekọja na, kì iṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ. Ṣugbọn Hesekiah bẹ̀bẹ fun wọn, wipe, Oluwa, ẹni-rere, dariji olukuluku, 19 Ti o mura ọkàn rẹ̀ lati wá Ọlọrun, Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀, ṣugbọn ti kì iṣe nipa ìwẹnumọ́ mimọ́. 20 Oluwa si gbọ́ ti Hesekiah, o si mu awọn enia na lara dá. 21 Awọn ọmọ Israeli ti a ri ni Jerusalemu fi ayọ̀ nla pa ajọ àkara alaiwu mọ́ li ọjọ meje: awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa yìn Oluwa lojojumọ, nwọn nfi ohun-elo olohùn goro kọrin si Oluwa. 22 Hesekiah sọ̀rọ itunu fun gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o loye ni ìmọ rere Oluwa: ijọ meje ni nwọn fi jẹ àse na, nwọn nru ẹbọ alafia, nwọn si nfi ohùn rara dupẹ fun Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.

Ayẹyẹ Ẹẹkeji

23 Gbogbo ijọ na si gbìmọ lati pa ọjọ meje miran mọ́: nwọn si fi ayọ̀ pa ọjọ meje miran mọ́. 24 Nitori Hesekiah, ọba Juda, ta ijọ enia na li ọrẹ, ẹgbẹrun akọ-malu, ati ẹ̃dẹgbãrun àgutan: ọ̀pọlọpọ ninu awọn alufa si yà ara wọn si mimọ́. 25 Gbogbo ijọ-enia Juda pẹlu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo ijọ-enia ti o ti inu Israeli jade wá, ati awọn àlejo ti o ti ilẹ Israeli jade wá, ati awọn ti ngbe Juda yọ̀. 26 Bẹ̃li ayọ̀ nla si wà ni Jerusalemu: nitori lati ọjọ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, iru eyi kò sí ni Jerusalemu. 27 Nigbana li awọn alufa, awọn ọmọ Lefi dide, nwọn si sure fun awọn enia na: a si gbọ́ ohùn wọn, adura wọn si gòke lọ si ibugbe mimọ́ rẹ̀, ani si ọrun.

2 Kronika 31

Hesekaya Ṣe Àtúnṣe Ẹ̀sìn

1 NJẸ nigbati gbogbo eyi pari, gbogbo Israeli ti a ri nibẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, nwọn si fọ́ awọn ere tũtu, nwọn si bẹ́ igbo òriṣa lulẹ, nwọn si bì ibi giga wọnni ati awọn pẹpẹ ṣubu, ninu gbogbo Juda ati Benjamini, ni Efraimu pẹlu ati Manasse, titi nwọn fi pa gbogbo wọn run patapata. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli yipada, olukuluku si ilẹ-ini rẹ̀ si ilu wọn. 2 Hesekiah si yàn ipa awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi nipa ipa wọn, olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ sisun, ati fun ẹbọ-alafia lati ṣiṣẹ, ati lati dupẹ, ati lati ma yìn li ẹnu-ọ̀na ibudo Oluwa. 3 Ọba si fi ipin lati inu ini rẹ̀ sapakan fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ sisun orowurọ ati alalẹ, ati ẹbọ sisun ọjọjọ isimi, ati fun oṣù titun, ati fun ajọ ti a yàn, bi a ti kọ ọ ninu ofin Oluwa. 4 Pẹlupẹlu o paṣẹ fun awọn enia ti ngbe Jerusalemu lati fi ipin kan fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin. 5 Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ. 6 Ati awọn ọmọ Israeli ati Juda, ti ngbe inu ilu Juda wọnni, awọn pẹlu mu idamẹwa malu ati agutan wá ati idamẹwa gbogbo ohun mimọ́ ti a yà si mimọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kó wọn jọ li òkiti òkiti. 7 Li oṣù kẹta, nwọn bẹ̀rẹ si ifi ipilẹ awọn òkiti lelẹ, nwọn si pari rẹ̀ li oṣù keje. 8 Nigbati Hesekiah ati awọn ijoye de, ti nwọn si ri òkiti wọnni, nwọn fi ibukún fun Oluwa, ati Israeli enia rẹ̀. 9 Hesekiah si bère lọdọ awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi niti òkiti wọnni. 10 Asariah, olori alufa ti ile Sadoku, si da a lohùn o si wipe, Lati igba ti awọn enia bẹ̀rẹ si imu ọrẹ wá sinu ile Oluwa, awa ní to lati jẹ, a si kù pupọ silẹ: Oluwa sa ti bukún awọn enia rẹ̀; eyiti o kù ni iṣura nla yi. 11 Nigbana ni Hesekiah paṣẹ lati pèse iyàrá-iṣura ni ile Ọlọrun; nwọn si pèse wọn. 12 Nwọn si mu awọn ọrẹ ati idamẹwa ati ohun ti a yà si mimọ́ wọ̀ ile wá nitõtọ: lori eyiti Kononiah, ọmọ Lefi, nṣe olori, Ṣimei arakunrin rẹ̀ si ni igbakeji. 13 Ati Jehieli, ati Asasiah, ati Nahati, ati Asaheli, ati Jerimoti, ati Josabadi, ati Elieli, ati Ismakiah, ati Mahati, ati Benaiah, ni awọn alabojuto labẹ ọwọ Kononiah ati Ṣimei arakunrin rẹ̀, nipa aṣẹ Hesekiah ọba, ati Asariah, olori ile Ọlọrun. 14 Ati Kore, ọmọ Imna, ọmọ Lefi, adèna iha ila-õrun, li o wà lori awọn ọrẹ atinuwa Ọlọrun, lati pin ẹbọ ọrẹ Oluwa, ati ohun mimọ́ julọ. 15 Ati labẹ ọwọ rẹ̀ ni Edeni, ati Miniamini, ati Jeṣua, ati Ṣemaiah, Amariah, ati Ṣekaniah, ninu ilu awọn alufa, lati fun awọn arakunrin wọn li ẹsẹsẹ, li otitọ, bi fun ẹni-nla, bẹ̃ni fun ẹni-kekere. 16 Laika awọn ọkunrin, ti a kọ sinu iwe idile, lati ọmọ ọdun mẹta ati jù bẹ̃ lọ, fun olukuluku wọn ti o nwọ̀ inu ile Oluwa lọ, ìwọn tirẹ̀ lojojumọ, fun iṣẹ ìsin wọn, ninu ilana wọn, gẹgẹ bi ipa wọn; 17 Ati fun awọn alufa ti a kọ sinu iwe nipa ile baba wọn, ati awọn ọmọ Lefi, lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ, ninu ilana wọn, nipa ipa wọn: 18 Ati fun awọn ti a kọ sinu iwe, gbogbo awọn ọmọ kekeke wọn, awọn aya wọn, ati awọn ọmọkunrin wọn, ati awọn ọmọbinrin wọn, ja gbogbo ijọ enia na: nitori ninu otitọ ni nwọn yà ara wọn si mimọ́ ninu iṣẹ mimọ́. 19 Ati fun awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ti o wà li oko igberiko ilu wọn ni olukuluku ilu, awọn ọkunrin wà nibẹ, ti a pè li orukọ, lati ma fi fun gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa, ati fun gbogbo awọn ti a kà ni idile idile ninu awọn ọmọ Lefi. 20 Bayi ni Hesekiah si ṣe ni gbogbo Juda, o si ṣe eyiti o dara, ti o si tọ́, ti o si ṣe otitọ, niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀. 21 Ati ninu gbogbo iṣẹ ti o bẹ̀rẹ ninu iṣẹ-ìsin ile Ọlọrun, ati ninu ofin, ati ni aṣẹ, lati wá Ọlọrun, o fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe e, o si ṣe rere.

2 Kronika 32

Asiria Halẹ̀ Mọ́ Jerusalẹmu

1 LẸHIN ti a ti ṣe iṣẹ wọnyi lotitọ, Sennakeribu, ọba Assiria, de, o si wọ̀ inu Juda lọ, o si dótì awọn ilu olodi, o si rò lati gbà wọn fun ara rẹ̀. 2 Nigbati Hesekiah ri pe Sennakeribu de, ti o fi oju si ati ba Jerusalemu jagun, 3 O ba awọn ijoye rẹ̀ ati awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ gbìmọ, lati dí omi orisun wọnni, ti mbẹ lẹhin ilu: nwọn si ràn a lọwọ. 4 Bẹ̃li ọ̀pọlọpọ enia kojọ pọ̀, awọn ẹniti o dí gbogbo orisun, ati odò ti nṣàn la arin ilẹ na ja, wipe, Nitori kili awọn ọba Assiria yio ṣe wá, ki nwọn ki o si ri omi pupọ̀? 5 O mu ara rẹ̀ le pẹlu, o si mọ gbogbo odi ti o ti ya, o si gbé e ga de awọn ile-iṣọ, ati odi miran lode, o si tun Millo ṣe ni ilu Dafidi, o si ṣe ọ̀kọ ati apata li ọ̀pọlọpọ. 6 O si yàn awọn balogun lori awọn enia, o si kó wọn jọ pọ̀ sọdọ rẹ̀ ni ita ẹnu-bode ilu, o si sọ̀rọ iyanju fun wọn, wipe, 7 Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe onigboya, ẹ má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò nyin nitori ọba Assiria, tabi nitori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀; nitori awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rẹ̀ lọ: 8 Apa ẹran-ara li o pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa. Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọ̀rọ Hesekiah, ọba Juda. 9 Lẹhin eyi ni Sennakeribu, ọba Assiria, rán awọn iranṣẹ si Jerusalemu, (ṣugbọn on tikararẹ̀ dótì Lakiṣi ati gbogbo ogun rẹ̀ pẹlu rẹ̀) sọdọ Hesekiah, ọba Juda ati sọdọ gbogbo Juda ti o wà ni Jerusalemu wipe, 10 Bayi ni Sennakeribu, ọba Assiria, wi pe, Kili ẹnyin gbẹkẹle, ti ẹnyin joko ninu odi agbara ni Jerusalemu? 11 Kò ṣepe Hesekiah ntàn nyin lati fi ara nyin fun ikú, nipa ìyan, ati nipa ongbẹ, o nwipe, Oluwa, Ọlọrun wa, yio gbà wa lọwọ ọba Assiria? 12 Kò ṣepe Hesekiah kanna li o mu ibi giga rẹ̀ wọnni kuro, ati pẹpẹ rẹ̀, ti o si paṣẹ fun Juda ati Jerusalemu, wipe, Ki ẹnyin ki o mã sìn niwaju pẹpẹ kan, ki ẹnyin ki o mã sun turari lori rẹ̀? 13 Enyin kò ha mọ̀ ohun ti emi ati awọn baba mi ti ṣe si gbogbo enia ilẹ miran? awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ilẹ wọnni ha le gbà ilẹ wọn lọwọ mi rara? 14 Tani ninu gbogbo awọn oriṣa orilẹ-ède wọnni, ti awọn baba mi parun tũtu, ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ti Ọlọrun nyin yio fi le gbà nyin lọwọ mi? 15 Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o tàn nyin jẹ, bẹ̃ni ki o máṣe rọ̀ nyin bi iru eyi, bẹ̃ni ki ẹ máṣe gbà a gbọ́: nitoriti kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ati lọwọ awọn baba mi: ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi? 16 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ jù bẹ̃ lọ si Oluwa Ọlọrun, ati si iranṣẹ rẹ̀, Hesekiah. 17 O kọ iwe pẹlu lati kẹgan Oluwa, Ọlọrun Israeli, ati lati sọ̀rọ òdi si i, wipe, Gẹgẹ bi awọn oriṣa orilẹ-ède ilẹ miran kò ti gbà awọn enia wọn lọwọ mi, bẹ̃li Ọlọrun Hesekiah kì yio gbà awọn enia rẹ̀ lọwọ mi. 18 Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara li ède Juda si awọn enia Jerusalemu ti mbẹ lori odi, lati dẹruba wọn, ati lati dãmu wọn; ki nwọn ki o le kó ilu na. 19 Nwọn si sọ̀rọ òdi si Ọlọrun Jerusalemu, bi ẹnipe si awọn oriṣa enia ilẹ aiye, ti iṣe iṣẹ ọwọ enia. 20 Ati nitori eyi ni Hesekiah, ọba, ati Isaiah woli, ọmọ Amosi, gbadura, nwọn si kigbe si ọrun. 21 Oluwa si rán Angeli kan, ẹniti o pa gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣãju, ati awọn balogun ni ibudo ọba Assiria. Bẹ̃li o fi itiju pada si ilẹ on tikararẹ̀. Nigbati o si wá sinu ile oriṣa rẹ̀, awọn ti o ti inu ara rẹ̀ jade si fi idà pa a nibẹ. 22 Bayi li Oluwa gbà Hesekiah ati awọn ti ngbe Jerusalemu lọwọ Sennakeribu ọba Assiria, ati lọwọ gbogbo awọn omiran, o si ṣọ́ wọn ni iha gbogbo. 23 Ọ̀pọlọpọ si mu ẹ̀bun fun Oluwa wá si Jerusalemu, ati ọrẹ fun Hesekiah, ọba Juda: a si gbé e ga loju gbogbo orilẹ-ède lẹhin na.

Àìsàn ati Ìgbéraga Hesekaya

24 Li ọjọ wọnni, Hesekiah ṣe aisan de oju ikú, o si gbadura si Oluwa; O si da a lohùn, O si fi àmi kan fun u. 25 Ṣugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rẹ̀ gbega: nitorina ni ibinu ṣe wà lori rẹ̀, lori Juda, ati lori Jerusalemu. 26 Ṣugbọn Hesekiah rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, niti igberaga ọkàn rẹ̀, ati on ati awọn ti ngbe Jerusalemu, bẹ̃ni ibinu Oluwa kò wá sori wọn li ọjọ Hesekiah.

Ọrọ̀ ati Ògo Hesekaya

27 Hesekiah si li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ ati ọlá: o si ṣe ibi-iṣura fun ara rẹ̀ fun fadakà, ati fun wura, ati fun okuta iyebiye, ati fun turari ati fun apata, ati fun oniruru ohun-elo iyebiye. 28 Ile-iṣura pẹlu fun ibisi ọkà, ati ọti-waini; ati ororo; ati ile fun gbogbo oniruru ẹran, ati ọgbà fun agbo-ẹran. 29 Pẹlupẹlu o ṣe ilu fun ara rẹ̀, ati agbo agutan ati agbo malu li ọ̀pọlọpọ: nitoriti Ọlọrun fun u li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ. 30 Hesekiah kanna yi li o dí ipa-omi ti o wà li òke Gihoni pẹlu, o si mu u wá isalẹ tara si iha iwọ-õrun ilu Dafidi. Hesekiah si ṣe rere ni gbogbo iṣẹ rẹ̀. 31 Ṣugbọn niti awọn ikọ̀ awọn ọmọ-alade Babeli, ti nwọn ranṣẹ si i, lati bère ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na, Ọlọrun fi i silẹ lati dán a wò, ki o le mọ̀ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Hesekaya

32 Ati iyokù iṣe Hesekiah ati iṣẹ rere rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe iran Isaiah woli, ọmọ Amosi, ani ninu iwe awọn ọba Juda ati Israeli. 33 Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sin i ninu iboji awọn ọmọ Dafidi: ati gbogbo Juda ati awọn ti ngbe Jerusalemu ṣe ẹyẹ fun u ni iku rẹ̀. Manasse ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 33

Manase, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mejila ni Manasse, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu: 2 Ṣugbọn o ṣe buburu li oju Oluwa, bi irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli. 3 Nitori ti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀, ti wó lulẹ, o si gbé pẹpẹ wọnni soke fun Baalimu, o si ṣe ere oriṣa, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn. 4 O tẹ́ pẹpẹ pẹlu ni ile Oluwa, niti eyiti Oluwa ti sọ pe; Ni Jerusalemu li orukọ mi yio wà lailai. 5 O si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li àgbala mejeji ile Oluwa. 6 O si mu ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná àfonifoji ọmọ Hinnomu: ati pẹlu o nṣe akiyesi afọṣẹ, o si nlò alupayida, o si nṣe ajẹ́, o si mba okú lò, ati pẹlu oṣó: o ṣe buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu. 7 O si gbé ere gbigbẹ kalẹ, ere ti o ti yá sinu ile Ọlọrun, niti eyiti Ọlọrun ti sọ fun Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀, pe, Ninu ile yi, ati ni Jerusalemu ti emi ti yàn ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai: 8 Bẹ̃li emi kì yio ṣi ẹsẹ Israeli mọ kuro ni ilẹ na ti emi ti yàn fun awọn baba nyin; kiki bi nwọn ba ṣe akiyesi lati ṣe gbogbo eyiti emi ti pa li aṣẹ fun wọn, gẹgẹ bi gbogbo ofin ati aṣẹ ati ilana lati ọwọ Mose wá. 9 Bẹ̃ni Manasse mu ki Judah ati awọn ti ngbe Jerusalemu ki o yapa, ati lati ṣe buburu jù awọn orilẹ-ède lọ, awọn ẹniti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli.

Manase Ronupiwada

10 Oluwa si ba Manasse wi ati awọn enia rẹ̀; ṣugbọn nwọn kò kiyesi i. 11 Nitorina li Oluwa mu awọn balogun ogun Assiria wá ba wọn, ti nwọn fi ìwọ mu Manasse, nwọn si de e li ẹ̀wọn, nwọn mu u lọ si Babeli. 12 Nigbati o si wà ninu wahala, o bẹ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ gidigidi niwaju Ọlọrun awọn baba rẹ̀, 13 O si gbadura si i: Ọlọrun si gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, o si tun mu u pada wá si Jerusalemu sinu ijọba rẹ̀. Nigbana ni Manasse mọ̀ pe: Oluwa, On li Ọlọrun. 14 Njẹ lẹhin eyi, o mọ odi kan lẹhin ilu Dafidi, niha ìwọ-õrun Gihoni, li àfonifoji, ani li atiwọ ẹnu-bode ẹja, o si yi Ofeli ka, o si mọ ọ ga soke gidigidi, o si fi balogun sinu gbogbo ilú olodi Juda wọnni. 15 O si kó awọn àjeji ọlọrun ati ere kuro ni ile Oluwa, ati gbogbo pẹpẹ ti o ti tẹ́ lori òke ile Oluwa ati ni Jerusalemu, o si kó wọn danu kuro ni ilu. 16 O si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, o si rú ẹbọ alafia ati ẹbọ ọpẹ lori rẹ̀, o si paṣẹ fun Juda lati ma sìn Oluwa Ọlọrun Israeli. 17 Sibẹ awọn enia nṣe irubọ ni ibi giga wọnni, kiki si Oluwa, Ọlọrun wọn nikan ni.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Manase

18 Ati iyokù iṣe Manasse, ati adura rẹ̀ si Ọlọrun rẹ̀, ati ọ̀rọ awọn ariran ti o ba a sọ̀rọ li orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli, kiye si i, o wà ninu iwe ọba Israeli. 19 Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai. 20 Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i si ile on tikalarẹ̀: Amoni, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Amoni, Ọba Juda

21 Ẹni ọdun mejidilogun ni Amoni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun meji ni Jerusalemu. 22 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi Manasse, baba rẹ̀ ti ṣe, nitori Amoni rubọ si gbogbo awọn ere yiyá, ti Manasse baba rẹ̀ ti ṣe, o si sìn wọn: 23 Kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Oluwa bi Manasse, baba rẹ̀, ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; ṣugbọn Amoni dẹṣẹ pupọpupọ. 24 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nwọn si pa a ni ile rẹ̀. 25 Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o ti di rikiṣi si Amoni, ọba; awọn enia ilẹ na si fi Josiah, ọmọ rẹ̀, jọba ni ipò rẹ̀.

2 Kronika 34

Josaya, Ọba Juda

1 ẸNI ọdun mẹjọ, ni Josiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanlelọgbọn ni Jerusalemu. 2 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, o si rìn li ọ̀na Dafidi, baba rẹ̀, kò si yà si ọwọ ọtún tabi si òsi.

Josaya Gbógun ti Ìwà Ìbọ̀rìṣà

3 Nitori li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀, nigbati o si wà li ọdọmọde sibẹ, o bẹ̀rẹ si iwá Ọlọrun Dafidi, baba rẹ̀; ati li ọdun kejila, o bẹ̀rẹ si iwẹ̀ Juda ati Jerusalemu mọ́ kuro ninu ibi giga wọnni, ati ere-oriṣa, ati ere yiyá, ati ere didà. 4 Nwọn si wó pẹpẹ Baalimu lulẹ niwaju rẹ̀; ati awọn ere õrun ti o wà lori wọn li o ké lulẹ; ati awọn ere-oriṣa, ati awọn ere yiyá, ati awọn ere didà, li o fọ tũtu, o sọ wọn di ekuru, o si gbọ̀n ọ sori isa-okú awọn ti o ti nrubọ́ si wọn. 5 O si sun egungun awọn alufa-oriṣa lori pẹpẹ wọn; o si wẹ Juda ati Jerusàlemu mọ́. 6 Bẹ̃li o si ṣe ni ilu Manasse wọnni ati ti Efraimu, ati ti Simeoni, ani titi de Naftali, o tú ile wọn yikakiri. 7 Nigbati o si fọ́ awọn pẹpẹ ati ère-oriṣa dilẹ, ti o si ti gún awọn ere yiyá di ẹ̀tu, ti o si ti ké gbogbo awọn ère-õrun lulẹ ni gbogbo ilẹ Israeli, o pada si Jerusalemu.

Wọ́n Rí Ìwé Òfin

8 Njẹ li ọdun kejidilogun ijọba rẹ̀, nigbati o ti wẹ̀ ilẹ na mọ́, ati ile na, o rán Ṣafani, ọmọ Asaliah, ati Maaseiah, olori ilu na, ati Joa, ọmọ Joahasi, akọwe iranti, lati tun ile Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ṣe. 9 Nigbati nwọn si de ọdọ Hilkiah, olori alufa, nwọn fi owo na ti a mu wá sinu ile Ọlọrun le e lọwọ, ti awọn ọmọ Lefi, ti o ntọju ilẹkun, ti kójọ lati ọwọ Manasse ati Efraimu, ati lati ọdọ gbogbo awọn iyokù Israeli, ati lati gbogbo Juda ati Benjamini: nwọn si pada si Jerusalemu. 10 Nwọn si fi i le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto iṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi i fun awọn aṣiṣẹ ti nṣiṣẹ ile Oluwa, lati tun ile na ṣe: 11 Awọn ọlọnà ati awọn kọlekọle ni nwọn fifun lati ra okuta gbigbẹ́, ati ìti-igi fun isopọ̀, ati lati tẹ́ ile wọnni ti awọn ọba Juda ti bajẹ. 12 Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin. 13 Nwọn si wà lori awọn alãru, ati awọn alabojuto gbogbo awọn ti nṣiṣẹ, ninu ìsinkisin ati ninu awọn ọmọ Lefi ni akọwe, ati olutọju ati adèna. 14 Nigbati nwọn si mu owo na ti a mu wá sinu ile Oluwa jade wá, Hilkiah alufa, ri iwe ofin Oluwa ti a ti ọwọ Mose kọ. 15 Hilkiah si dahùn o si wi fun Ṣafani, akọwe, pe, Emi ri iwe ofin ninu ile Oluwa, Hilkiah si fi iwe na le Ṣafani lọwọ. 16 Ṣafani si mu iwe na tọ̀ ọba lọ, o si mu èsi pada fun ọba wá wipe, Gbogbo eyi ti a fi le awọn iranṣẹ rẹ lọwọ, nwọn ṣe e. 17 Nwọn si ti kó gbogbo owo ti a ri ni ile Oluwa jọ, nwọn si ti fi le ọwọ awọn alabojuto, ati le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ. 18 Nigbana ni Ṣafani, akọwe, wi fun ọba pe, Hilkiah alufa, fun mi ni iwe kan. Ṣafani si kà a niwaju ọba. 19 O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ ofin na, o si fa aṣọ rẹ̀ ya. 20 Ọba si paṣẹ fun Hilkiah ati Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Abdoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọwe, ati Asaiah, iranṣẹ ọba, wipe, 21 Ẹ lọ, ẹ bere lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn ti o kù ni Israeli ati ni Juda, niti ọ̀rọ iwe ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti a tú jade sori wa, nítori awọn bàba wa kò pa ọ̀rọ Oluwa mọ́, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu iwe yi. 22 Ati Hilkiah, ati awọn ti ọba ti yàn tọ̀ Hulda, woli obinrin, lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikehati, ọmọ Hasra, olutọju aṣọ (njẹ, o ngbe Jerusalemu, niha keji;) nwọn si ba a sọ̀rọ na. 23 O si dá wọn lohùn pe, Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ sọ fun ọkunrin na ti o rán nyin si mi pe, 24 Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi wá si ihinyi ati si awọn ti ngbe ibẹ na, ani gbogbo egún ti a kọ sinu iwe ti nwọn ti kà niwaju ọba Juda: 25 Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti sun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina li a o ṣe tú ibinu mi sori ihinyi, a kì yio si paná rẹ̀. 26 Bi o si ṣe ti ọba Juda nì, ẹniti o rán nyin lati bère lọwọ Oluwa, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́: 27 Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun, nigbati iwọ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ si ihinyi, ati si awọn ti ngbe ibẹ, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi, ti iwọ si fa aṣọ rẹ ya, ti iwọ si sọkun niwaju mi; ani emi ti gbọ́ tirẹ pẹlu, li Oluwa wi. 28 Kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ si isa-okú rẹ li alafia, bẹ̃ni oju rẹ kì yio ri gbogbo ibi ti emi o mu wá si ihinyi, ati sori awọn ti ngbe ibẹ. Bẹ̃ni nwọn mu èsi pada fun ọba wá.

Josaya Dá Majẹmu láti Tẹ̀lé OLUWA

29 Nigbana ni ọba ranṣẹ, nwọn si kó gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ. 30 Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo ọkunrin Juda, ati awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo enia ati ẹni-nla ati ẹni-kekere: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn. 31 Ọba si duro ni ipò rẹ̀, o si dá majẹmu niwaju Oluwa lati ma fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati ṣe ọ̀rọ majẹmu na ti a kọ sinu iwe yi. 32 O si mu ki gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ati Benjamini duro ninu rẹ̀, awọn ti ngbe Jerusalemu si ṣe gẹgẹ bi majẹmu Ọlọrun, Ọlọrun awọn baba wọn. 33 Josiah si kó gbogbo ohun-irira kuro ninu gbogbo ilu ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, o si mu ki gbogbo awọn ti o wà ni Israeli ki o sìn, ani ki nwọn sìn Oluwa Ọlọrun wọn. Ati li ọjọ rẹ̀ gbogbo nwọn kò yà kuro lati ma tọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, lẹhin.

2 Kronika 35

Josaya Pa Àjọ Ìrékọjá Mọ́

1 JOSIAH si pa irekọja kan mọ́ si Oluwa ni Jerusalemu: nwọn si pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù kini. 2 O si yàn awọn alufa si iṣẹ wọn, o si gbà wọn ni iyanju si ìsin ile Oluwa. 3 O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀; 4 Ẹ si mura nipa ile awọn baba nyin, li ẹsẹsẹ nyin, gẹgẹ bi iwe Dafidi, ọba Israeli, ati gẹgẹ bi iwe Solomoni, ọmọ rẹ̀. 5 Ẹ si duro ni ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi ipin idile awọn baba arakunrin nyin, awọn enia na, ati bi ipin idile awọn ọmọ Lefi. 6 Bẹ̃ni ki ẹ pa ẹran irekọja na, ki ẹ si yà ara nyin si mimọ́, ki ẹ si mura fun awọn arakunrin nyin, ki nwọn ki o le mã ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Mose. 7 Josiah si fun awọn enia na, ni ọdọ-agutan ati ọmọ ewurẹ, lati inu agbo-ẹran, gbogbo rẹ̀ fun ẹbọ irekọja na, fun gbogbo awọn ti o wà nibẹ, iye rẹ̀ ẹgbã mẹdogun, ati ẹgbẹdogun akọmalu: lati inu ini ọba ni wọnyi. 8 Awọn ijoye rẹ̀ si fi tinutinu ta awọn enia li ọrẹ, fun awọn alufa, ati fun awọn ọmọ Lefi: Hilkiah ati Sekariah ati Jehieli, awọn olori ile Ọlọrun, si fun awọn alufa fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹtala ẹran-ọ̀sin kekeke, ati ọ̃dunrun malu. 9 Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu. 10 Bẹ̃li a si mura ìsin na, awọn alufa si duro ni ipò wọn, ati awọn ọmọ Lefi ni ipa iṣẹ wọn gẹgẹ bi aṣẹ ọba. 11 Awọn ọmọ Lefi si pa ẹran irekọja na, awọn alufa si wọ́n ẹ̀jẹ na lati ọwọ wọn wá, awọn ọmọ Lefi si bó wọn. 12 Nwọn si yà awọn ẹbọ-sisun sapakan, ki nwọn ki o le pin wọn funni gẹgẹ bi ipin idile awọn enia, lati rubọ si Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose. Bẹ̃ni nwọn si ṣe awọn malu pelu. 13 Nwọn si fi iná sun irekọja na gẹgẹ bi ilana na: ṣugbọn awọn ẹbọ mimọ́ iyokù ni nwọn bọ̀ ninu ìkoko, ati ninu òdu ati ninu agbada, nwọn si pin i kankan fun gbogbo enia. 14 Lẹhin na nwọn mura silẹ fun ara wọn, ati fun awọn alufa; nitoriti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, wà ni riru ẹbọ sisun ati ọ̀ra titi di alẹ; nitorina awọn ọmọ Lefi mura silẹ fun ara wọn ati fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni. 15 Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn. 16 Bẹ̃ni a si mura gbogbo ìsin Oluwa li ọjọ kanna, lati pa irekọja mọ́, ati lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ Oluwa, gẹgẹ bi ofin Josiah, ọba. 17 Ati awọn ọmọ Israeli ti a ri nibẹ, pa irekọja na mọ́ li akoko na, ati ajọ aiwukara li ọjọ meje. 18 Kò si si irekọja kan ti o dabi rẹ̀ ti a ṣe ni Israeli lati igba ọjọ Samueli woli; bẹ̃ni gbogbo awọn ọba Israeli kò pa iru irekọja bẹ̃ mọ́, bi eyi ti Josiah ṣe, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Juda ati Israeli ti a ri nibẹ, ati awọn ti ngbe Jerusalemu. 19 Li ọdun kejidilogun ijọba Josiah li a pa irekọja yi mọ́.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya

20 Lẹhin gbogbo eyi, ti Josiah ti tun ile na ṣe tan, Neko, ọba Egipti, gòke wá, si Karkemiṣi lẹba odò Euferate: Josiah si jade tọ̀ ọ. 21 Ṣugbọn o rán ikọ̀ si i, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, iwọ ọba Juda? Emi kò tọ̀ ọ wá loni, bikòṣe si ile ti mo ba ni ijà: Ọlọrun sa pa aṣẹ fun mi lati yara: kuro lọdọ Ọlọrun, ẹniti o wà pẹlu mi, ki on má ba pa ọ run. 22 Ṣugbọn Josiah kò yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ rẹ̀, ṣugbọn o pa aṣọ ara rẹ dà, ki o le ba a jà, kò si fi eti si ọ̀rọ Neko lati ẹnu Ọlọrun wá, o si wá ijagun li àfonifoji Megiddo. 23 Awọn tafatafa si ta Josiah, ọba: ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ gbé mi kuro; nitoriti mo gbà ọgbẹ gidigidi. 24 Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah. 25 Jeremiah si pohùn rere ẹkún fun Josiah, ati gbogbo awọn akọrin ọkunrin, ati awọn akọrin obinrin, si nsọ ti Josiah ninu orin-ẹkún wọn titi di oni yi, nwọn si sọ wọn di àṣa kan ni Israeli; si kiyesi i, a kọ wọn ninu awọn orin-ẹkún. 26 Ati iyokú iṣe Josiah, ati ìwa rere rẹ̀, gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu ofin Oluwa, 27 Ati iṣe rẹ̀, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Judah.

2 Kronika 36

Joahasi, ọba Juda

1 NIGBANA ni awọn enia ilẹ na mu Jehoahasi, ọmọ Josiah, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀ ni Jerusalemu. 2 Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣu mẹta ni Jerusalemu. 3 Ọba Egipti si mu u kuro ni Jerusalemu, o si bù ọgọrun fadakà ati talenti wura kan fun ilẹ na. 4 Ọba Egipti si fi Eliakimu, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu; Neko si mu Jehoahasi, arakunrin rẹ̀, o si mu u lọ si Egipti.

Jehoiakimu, Ọba Juda

5 Ẹni ọdun mẹdọgbọn ni Jehoiakimu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu; o si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, 6 Nebukadnessari, ọba Babeli, gòke wá, o si dè e ni ẹ̀won, lati mu u lọ si Babeli. 7 Nebukadnessari kó ninu ohun-elo ile Oluwa lọ si Babeli pẹlu, o si fi wọn sinu ãfin rẹ̀ ni Babeli. 8 Ati iyokù iṣe Jehoiakimu ati awọn ohun-irira rẹ̀ ti o ti ṣe, ti a si ri ninu rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda: Jehoiakini, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Jehoiakini, Ọba Juda

9 Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣù mẹta ati ijọ mẹwa ni Jerusalemu: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa. 10 Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu.

Sedekaya, Ọba Juda

11 Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. 12 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Jeremiah, woli, ti o sọ̀rọ lati ẹnu Oluwa wá.

Ìṣubú Jerusalẹmu

13 On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli. 14 Pẹlupẹlu, gbogbo awọn olori awọn alufa ati awọn enia dẹṣẹ gidigidi bi gbogbo irira awọn orilẹ-ède, nwọn si sọ ile Oluwa di ẽri, ti on ti yà si mimọ́ ni Jerusalemu. 15 Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn si ranṣẹ si wọn lati ọwọ awọn onṣẹ rẹ̀, o ndide ni kùtukutu o si nranṣẹ, nitori ti o ni iyọ́nu si awọn enia rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀. 16 Ṣugbọn nwọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, nwọn si kẹgan ọ̀rọ rẹ̀, nwọn si fi awọn woli rẹ̀ ṣẹsin, titi ibinu Oluwa fi ru si awọn enia rẹ̀, ti kò fi si atunṣe. 17 Nitorina li o ṣe mu ọba awọn ara Kaldea wá ba wọn, ẹniti o fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn ni ile ibi-mimọ́ wọn, kò si ni iyọ́nu si ọdọmọkunrin tabi wundia, arugbo, tabi ẹniti o bà fun ogbó: on fi gbogbo wọn le e li ọwọ. 18 Ati gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun, nla ati kekere, ati iṣura ile Oluwa ati iṣura ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; gbogbo wọn li o mu wá si Babeli. 19 Nwọn si kun ile Ọlọrun, nwọn si wó odi Jerusalemu palẹ, nwọn si fi iná sun ãfin rẹ̀, nwọn si fọ́ gbogbo ohun-elo daradara rẹ̀ tũtu. 20 Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia: 21 Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.

Kirusi Pàṣẹ Pé Kí Àwọn Juu Pada

22 Li ọdun kini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ Oluwa lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba Persia, soke, ti o si ṣe ikede ni gbogbo ijọba rẹ̀, o si kọ iwe pẹlu, wipe, 23 Bayi ni Kirusi, ọba Persia, wi pe, Gbogbo ijọba aiye li Oluwa Ọlọrun fi fun mi, o si ti paṣẹ fun mi lati kọ́ ile kan fun on ni Jerusalemu, ti mbẹ ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo awọn enia rẹ̀? Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ki o pẹlu rẹ̀, ki o si gòke lọ.

Esra 1

Kirusi Ọba pàṣẹ pé kí Àwọn Juu Pada

1 LI ọdun ekini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ OLUWA lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, OLUWA rú ẹmi Kirusi, ọba Persia soke, ti o mu ki a kede yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, a si kọwe rẹ̀ pẹlu wipe, 2 Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda. 3 Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu. 4 Ati ẹnikẹni ti o kù lati ibikibi ti o ti ngbe, ki awọn enia ibugbe rẹ̀ ki o fi fadaka ràn a lọwọ, pẹlu wura, ati pẹlu ẹrù, ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, pẹlu ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu. 5 Nigbana ni awọn olori awọn baba Juda ati Benjamini dide, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu gbogbo awọn ẹniti Ọlọrun rú ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA ti o wà ni Jerusalemu. 6 Gbogbo awọn ti o wà li agbegbe wọn si fi ohun-èlo fadaka ràn wọn lọwọ, pẹlu wura, pẹlu ẹrù ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, ati pẹlu ohun iyebiye, li aika gbogbo ọrẹ atinuwa. 7 Kirusi ọba si ko ohun èlo ile OLUWA jade, ti Nebukadnessari ti ko jade lọ lati Jerusalemu, ti o si fi sinu ile ọlọrun rẹ̀; 8 Kirusi ọba Persia si ko wọnyi jade nipa ọwọ Mitredati, oluṣọ iṣura, o si ka iye wọn fun Ṣeṣbassari (Serubbabeli) bãlẹ Juda. 9 Iye wọn si li eyi: ọgbọn awo-pọ̀kọ wura, ẹgbẹrun awo-pọ̀kọ fadaka, ọbẹ mọkandilọgbọn, 10 Ọgbọn ago wura, ago fadaka iru ekeji, irinwo o le mẹwa, ohun èlo miran si jẹ ẹgbẹrun. 11 Gbogbo ohun-èlo wura ati ti fadaka jẹ ẹgbẹtadilọgbọn. Gbogbo wọnyi ni Ṣeṣbassari mu goke wá pẹlu awọn igbekun ti a mu goke lati Babiloni wá si Jerusalemu.

Esra 2

Àwọn tí Wọ́n Pada ti Ìgbèkùn Dé

1 WỌNYI li awọn ọmọ igberiko Juda ti o goke wa, lati inu igbèkun awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnessari, ọba Babiloni, ti ko lọ si Babiloni, ti nwọn si pada wá si Jerusalemu ati Juda, olukuluku si ilu rẹ̀: 2 Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin ninu awọn enia Israeli: 3 Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbọkanla o din mejidilọgbọn. 4 Awọn ọmọ Ṣefatiah, irinwo o din mejidilọgbọn. 5 Awọn ọmọ Ara, ẹgbẹrin o din mẹ̃dọgbọn. 6 Awọn ọmọ Pahati-Moabu ninu awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejila. 7 Awọn ọmọ Elamu, adọtalelẹgbẹfa o le mẹrin. 8 Awọn ọmọ Sattu, ọtadilẹgbẹ̀run, o le marun. 9 Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin. 10 Awọn ọmọ Bani, ojilelẹgbẹta, o le meji. 11 Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mẹtalelogun. 12 Awọn ọmọ Asgadi, ẹgbẹfa, o le mejilelogun. 13 Awọn ọmọ Adonikami ọtalelẹgbẹta o le mẹfa. 14 Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹrindilọgọta. 15 Awọn ọmọ Adini, adọtalenirinwo o le mẹrin. 16 Awọn ọmọ Ateri ti Hesekiah, mejidilọgọrun. 17 Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹta. 18 Awọn ọmọ Jora, mejilelãdọfa. 19 Awọn ọmọ Haṣumu igba o le mẹtalelogun. 20 Awọn ọmọ Gibbari, marundilọgọrun. 21 Awọn ọmọ Betlehemu, mẹtalelọgọfa. 22 Awọn enia Netofa, mẹrindilọgọta. 23 Awọn enia Anatotu, mejidilãdọje. 24 Awọn ọmọ Asmafeti, mejilelogoji. 25 Awọn ọmọ Kirjat-arimu, Kefira ati Beeroti ọtadilẹgbẹrin o le mẹta. 26 Awọn ọmọ Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun. 27 Awọn ọmọ Mikmasi, mejilelọgọfa. 28 Awọn enia Beteli ati Ai, igba o le mẹtalelogun. 29 Awọn ọmọ Nebo, mejilelãdọta. 30 Awọn ọmọ Magbiṣi mẹrindilọgọjọ. 31 Awọn ọmọ Elamu ekeji, ãdọtalelẹgbẹfa o le mẹrin. 32 Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo. 33 Awọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le marun, 34 Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun. 35 Awọn ọmọ Sanaa, egbejidilogun o le ọgbọn. 36 Awọn alufa; awọn ọmọ Jedaiah, ti idile Jeṣua, ogúndilẹgbẹrun o din meje. 37 Awọn ọmọ Immeri, ãdọtalelẹgbẹrun o le meji. 38 Awọn ọmọ Paṣuri, ojilelẹgbẹfa o le meje. 39 Awọn ọmọ Harimu, ẹgbẹrun o le mẹtadilogun. 40 Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua ati Kadmieli ti awọn ọmọ Hodafiah, mẹrinlelãdọrin. 41 Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdoje. 42 Awọn ọmọ awọn adena: awọn ọmọ Ṣalumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, gbogbo wọn jẹ, mọkandilogoje. 43 Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti. 44 Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Padoni. 45 Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Akkubu, 46 Awọn ọmọ Hagabu, awọn ọmọ Ṣalmai, awọn ọmọ Hanani; 47 Awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari, awọn ọmọ Reaiah, 48 Awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda, awọn ọmọ Gassamu, 49 Awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Pasea, awọn ọmọ Besai, 50 Awọn ọmọ Asna, awọn ọmọ Mehunimi, awọn ọmọ Nefusimi, 51 Awọn ọmọ Bakbuki, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Har-huri, 52 Awọn ọmọ Basluti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harṣa, 53 Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama, 54 Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa, 55 Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Peruda, 56 Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli, 57 Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Ami. 58 Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni, jẹ irinwo o din mẹjọ. 59 Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe: 60 Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ãdọtalelẹgbẹta o le meji. 61 Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Hakosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o fẹ ọkan ninu awọn ọmọ Barsillai obinrin, ara Gileadi li aya, a si pè e nipa orukọ wọn; 62 Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa. 63 Balẹ si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o má jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi dide pẹlu Urimu ati pẹlu Tummimu. 64 Apapọ gbogbo ijọ na, jẹ ẹgbã mọkanlelogun o le ojidinirinwo. 65 Li aika iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹbinrin wọn, ti o jẹ ẹgbẹrindilẹgbãrin o din mẹtalelọgọta: igba akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin li o si wà ninu wọn. 66 Ẹṣin wọn jẹ, ọtadilẹgbẹrin o din mẹrin; ibaka wọn, ojilugba o le marun. 67 Ibakasiẹ wọn, irinwo o le marundilogoji; kẹtẹkẹtẹ wọn, ẹgbẹrinlelọgbọn o din ọgọrin. 68 Ati ninu awọn olori awọn baba, nigbati nwọn de ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu, nwọn si ta ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun, lati gbe e duro ni ipò rẹ̀. 69 Nwọn fi sinu iṣura iṣẹ na gẹgẹ bi agbara wọn, ọkẹ mẹta ìwọn dramu wura, o le ẹgbẹrun, ẹgbẹdọgbọn mina fadaka, ati ọgọrun ẹ̀wu alufa. 70 Bẹ̃li awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati omiran ninu awọn enia, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, ati awọn Netinimu ngbe ilu wọn, gbogbo Israeli si ngbe ilu wọn.

Esra 3

Wọ́n tún Bẹ̀rẹ̀ Ìjọ́sìn

1 NIGBATI oṣu keje si pé, ti awọn ọmọ Israeli si wà ninu ilu wọnni, awọn enia na ko ara wọn jọ pọ̀ bi ẹnikan si Jerusalemu. 2 Jeṣua ọmọ Jehosadaki si dide pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ awọn alufa, ati Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si tẹ́ pẹpẹ Ọlọrun Israeli, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun lori rẹ̀, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, enia Ọlọrun. 3 Nwọn si gbe pẹpẹ na ka ipilẹ rẹ̀; nitori ẹ̀ru bà wọn nitori awọn enia ilẹ wọnni. Nwọn si rú ẹbọ ọrẹ sisun si Oluwa, ọrẹ ẹbọ sisun li owurọ ati li aṣalẹ. 4 Nwọn si pa àse agọ mọ pẹlu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, nwọn si rú ẹbọ sisun ojojumọ pẹlu nipa iye ti a pa li aṣẹ, gẹgẹ bi isin ojojumọ; 5 Lẹhin na nwọn si ru ẹbọ sisun igbagbogbo ati ti oṣu titun, ati ti gbogbo ajọ Oluwa, ti a si yà si mimọ́, ati ti olukuluku ti o fi tinu-tinu ru ẹbọ atinuwa si Oluwa. 6 Lati ọjọ ikini oṣu keje ni nwọn bẹ̀rẹ lati ma rú ẹbọ sisun si Oluwa. Ṣugbọn a kò ti ifi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ.

Títún Tẹmpili Kọ́ Bẹ̀rẹ̀

7 Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia. 8 Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa. 9 Nigbana ni Jeṣua pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, Kadmieli ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ Juda, jumọ dide bi ẹnikanṣoṣo lati ma tọju awọn oniṣẹ ninu ile Ọlọrun; awọn ọmọ Henadadi, pẹlu awọn ọmọ wọn, ati arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi. 10 Nigbati awọn ọmọle si fi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ, nwọn mu awọn alufa duro ninu aṣọ wọn, nwọn mu ipè lọwọ, ati awọn ọmọ Lefi, awọn ọmọ Asafu mu kimbali lọwọ, lati ma yìn Oluwa gẹgẹ bi ìlana Dafidi ọba Israeli. 11 Nwọn si jùmọ kọrin lẹsẹsẹ lati yìn ati lati dupẹ fun Oluwa, nitoripe o ṣeun, ati pe anu rẹ̀ si duro lailai lori Israeli. Gbogbo enia si ho iho nla, nigbati nwọn nyìn Oluwa, nitoriti a fi ipilẹ ile Oluwa lelẹ. 12 Ṣugbọn pupọ ninu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori awọn baba ti iṣe alàgba, ti nwọn ti ri ile atetekọṣe, nwọn fi ohùn rara sọkun, nigbati a fi ipilẹ ile yi lelẹ li oju wọn, ṣugbọn awọn pupọ si ho iho nla fun ayọ̀: 13 Tobẹ̃ ti awọn enia kò le mọ̀ iyatọ ariwo ayọ̀ kuro ninu ariwo ẹkun awọn enia; nitori awọn enia ho iho nla, a si gbọ́ ariwo na li okere rére.

Esra 4

Àtakò Sí Títún Ilé Ọlọrun Kọ́

1 NIGBATI awọn ọta Juda ati Benjamini gbọ́ pe awọn ọmọ-igbekun nkọ́ tempili fun Oluwa Ọlọrun Israeli; 2 Nigbana ni nwọn tọ̀ Serubbabeli wá, ati awọn olori awọn baba, nwọn si wi fun wọn pe, ẹ jẹ ki awa ki o ba nyin kọle, nitoriti awa nṣe afẹri Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin; awa si nru ẹbọ si ọdọ rẹ̀, lati ọjọ Esarhaddoni, ọba Assuri, ẹniti o mu wa gòke wá ihinyi. 3 Ṣugbọn Serubbabeli, ati Jeṣua ati iyokù ninu awọn olori awọn baba Israeli wi fun wọn pe, Kì iṣe fun awa pẹlu ẹnyin, lati jumọ kọ ile fun Ọlọrun wa; ṣugbọn awa tikarawa ni yio jùmọ kọle fun Oluwa Ọlọrun Israeli gẹgẹ bi Kirusi ọba, ọba Persia, ti paṣẹ fun wa, 4 Nigbana ni awọn enia ilẹ na mu ọwọ awọn enia Juda rọ, nwọn si yọ wọn li ẹnu ninu kikọle na. 5 Nwọn si bẹ̀ awọn ìgbimọ li ọ̀wẹ si wọn, lati sọ ipinnu wọn di asan, ni gbogbo ọjọ Kirusi, ọba Persia, ani titi di ijọba Dariusi, ọba Persia.

Àtakò sí Títún Jerusalẹmu Kọ́

6 Ati ni ijọba Ahasuerusi, ni ibẹ̀rẹ ijọba rẹ̀, ni nwọn kọwe ẹ̀sun lati fi awọn ara Juda ati Jerusalemu sùn. 7 Ati li ọjọ Artasasta ni Biṣlami, Mitredati, Tabeeli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ iyokù kọwe si Artasasta, ọba Persia: a si kọ iwe na li ède Siria, a si ṣe itumọ rẹ̀ li ède Siria. 8 Rehumu, adele ọba, ati Ṣimṣai, akọwe, kọ iwe ẹ̀sun Jerusalemu si Artasasta ọba, bi iru eyi: 9 Nigbana ni Rehumu, adele-ọba, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn iyokù: awọn ara Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, ti Arkefi, ti Babiloni, ti Susanki, ti Dehafi ati ti Elamu, 10 Ati awọn orilẹ-ède iyokù ti Asnapperi, ọlọla ati ẹni-nla nì, kó rekọja wá, ti o si fi wọn do si ilu Samaria, ati awọn iyokù ti o wà ni ihahin odò, ati ẹlomiran. 11 Eyi ni atunkọ iwe na ti nwọn fi ranṣẹ si i, ani si Artasasta ọba: Iranṣẹ rẹ, awọn enia ihahin odò ati ẹlomiran. 12 Ki ọba ki o mọ̀ pe, awọn Ju ti o ti ọdọ rẹ wá si ọdọ wa, nwọn de Jerusalemu, nwọn nkọ́ ọlọtẹ ilu ati ilu buburu, nwọn si ti fi odi rẹ̀ lelẹ, nwọn si ti so ipilẹ rẹ̀ mọra pọ̀. 13 Ki ọba ki o mọ̀ nisisiyi pe, bi a ba kọ ilu yi, ti a si tun odi rẹ̀ gbe soke tan, nigbana ni nwọn kì o san owo ori, owo-bode, ati owo odè, ati bẹ̃ni nikẹhin yio si pa awọn ọba li ara. 14 Njẹ nisisiyi lati ãfin ọba wá li a sa ti mbọ́ wa, kò si yẹ fun wa lati ri àbuku ọba, nitorina li awa ṣe ranṣẹ lati wi fun ọba daju; 15 Ki a le wá inu iwe-iranti awọn baba rẹ: bẹ̃ni iwọ o ri ninu iwe-iranti, iwọ o si mọ̀ pe, ọlọtẹ ni ilu yi, ti o si pa awọn ọba ati igberiko li ara, ati pe, nwọn ti ṣọtẹ ninu ikanna lati atijọ wá, nitori eyi li a fi fọ ilu na. 16 Awa mu u da ọba li oju pe, bi a ba tun ilu yi kọ, ti a si pari odi rẹ̀ nipa ọ̀na yi, iwọ kì o ni ipin mọ ni ihahin odò. 17 Nigbana ni ọba fi èsi ranṣẹ si Rehumu, adele-ọba, ati si Ṣimṣai, akọwe, pẹlu awọn ẹgbẹ wọn iyokù ti ngbe Samaria, ati si awọn iyokù li oke odò: Alafia! ati kiki miran. 18 A kà iwe ti ẹnyin fi ranṣẹ si wa dajudaju niwaju mi. 19 Mo si paṣẹ, a si ti wá, a si ri pe, lati atijọ wá, ilu yi a ti ma ṣọ̀tẹ si awọn ọba, ati pe irukerudo ati ọ̀tẹ li a ti nṣe ninu rẹ̀. 20 Pẹlupẹlu awọn ọba alagbara li o ti wà lori Jerusalemu, awọn ti o jọba lori gbogbo ilu oke-odò; owo ori, owo odè, ati owo bodè li a ti nsan fun wọn. 21 Ki ẹnyin ki o paṣẹ nisisiyi lati mu awọn ọkunrin wọnyi ṣiwọ, ki a má si kọ ilu na mọ, titi aṣẹ yio fi jade lati ọdọ mi wá. 22 Ẹ kiyesi ara nyin, ki ẹnyin ki o má jafara lati ṣe eyi: ẽṣe ti ìbajẹ yio fi ma dàgba si ipalara awọn ọba? 23 Njẹ nigbati a ka atunkọ iwe Artasasta ọba niwaju Rehumu, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn, nwọn gòke lọ kankán si Jerusalemu, si ọdọ awọn Ju, nwọn si fi ipá pẹlu agbara mu wọn ṣiwọ. 24 Nigbana ni iṣẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu, duro. Bẹ̃li o duro titi di ọdun keji Dariusi, ọba Persia.

Esra 5

Iṣẹ́ Kíkọ́ Tẹmpili Tún Bẹ̀rẹ̀

1 ṢUGBỌN awọn woli, Haggai woli, ati Sekariah ọmọ Iddo, sọ asọtẹlẹ fun awọn Ju ti o wà ni Juda ati Jerusalemu li orukọ Ọlọrun Israeli. 2 Li akoko na ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki dide, nwọn si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Ọlọrun ni Jerusalemu; awọn woli Ọlọrun si wà pẹlu wọn ti nràn wọn lọwọ. 3 Li akoko kanna ni Tatnai, bãlẹ ni ihahin odò, ati Ṣetar-bosnai pẹlu awọn ẹgbẹ wọn, wá si ọdọ wọn, nwọn si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati tun odi yi ṣe? 4 Nigbana ni awa wi fun wọn bayi, pe, Orukọ awọn ọkunrin ti nkọ́ ile yi ti ijẹ? 5 Ṣugbọn oju Ọlọrun wọn mbẹ li ara awọn àgba Juda, ti nwọn kò fi le mu wọn ṣiwọ titi ọ̀ran na fi de ọdọ Dariusi: nigbana ni nwọn si fi èsi pada, nipa iwe nitori eyi. 6 Atunkọ iwe da ti Tatnai, bãlẹ ni ihahin-odò, ati Ṣetar-bosnai, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ rán si Dariusi ọba: awọn ara Afarsaki ti ihahin-odò. 7 Nwọn fi iwe ranṣẹ si i, ninu eyiti a kọ bayi; Si Dariusi, ọba, alafia gbogbo. 8 Ki ọba ki o mọ̀ pe, awa lọ si igberiko Judea si ile Ọlọrun ẹniti o tobi, ti a fi okuta nlanla kọ, a si tẹ igi si inu ogiri na, iṣẹ yi nlọ siwaju kánkán, o si nṣe rere li ọwọ wọn. 9 Nigbana ni awa bi awọn àgba wọnni li ère, a si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati mọ odi yi? 10 Awa si bère orukọ wọn pẹlu, lati mu ki o da ọ li oju, ki a le kọwe orukọ awọn enia ti iṣe olori ninu wọn. 11 Bayi ni nwọn si fi èsi fun wa wipe, Iranṣẹ Ọlọrun ọrun on aiye li awa iṣe, awa si nkọ́ ile ti a ti kọ́ li ọdun pupọ wọnyi sẹhin, ti ọba nla kan ni Israeli ti kọ́, ti o si ti pari. 12 Ṣugbọn nitoriti awọn baba wa mu Ọlọrun ọrun binu, o fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babiloni ti Kaldea, ẹniti o wó ile yi palẹ, ti o si kó awọn enia na lọ si Babiloni. 13 Ṣugbọn li ọdun ekini Kirusi ọba Babiloni, Kirusi ọba na fi aṣẹ lelẹ lati kọ́ ile Ọlọrun yi. 14 Pẹlupẹlu ohun èlo wura ati ti fàdaka ti ile Ọlọrun ti Nebukadnessari ko lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si mu lọ sinu tempili Babiloni, awọn na ni Kirusi ọba ko lati inu tempili Babiloni jade, a si fi wọn le ẹnikan lọwọ, orukọ ẹniti ijẹ Ṣeṣbassari, ẹniti on fi jẹ bãlẹ; 15 On si wi fun u pe, Kó ohun èlo wọnyi lọ, ki o fi wọn si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, ki o si mu ki a tun kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀. 16 Nigbana ni Ṣeṣbassari na wá, o si fi ipilẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu lelẹ: ati lati igba na ani titi di isisiyi li o ti mbẹ, ni kikọ kò si ti ipari tan. 17 Njẹ nitorina, bi o ba wu ọba, jẹ ki a wá inu ile iṣura ọba ti o wà nibẹ ni Babiloni, bi o ba ri bẹ̃, pe Kirusi ọba fi aṣẹ lelẹ lati kọ ile Ọlọrun yi ni Jerusalemu, ki ọba ki o sọ eyi ti o fẹ fun wa nipa ọ̀ran yi.

Esra 6

Wọ́n Rí Àkọsílẹ̀ Àṣẹ tí Kirusi Ọba Pa

1 NIGBANA ni Dariusi ọba paṣẹ, a si wá inu ile ti a ko iwe jọ si, nibiti a to iṣura jọ si ni Babiloni. 2 A si ri iwe kan ni Ekbatana, ninu ilu olodi ti o wà ni igberiko Medea, ati ninu rẹ̀ ni iwe-iranti kan wà ti a kọ bayi: 3 Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ. 4 Ilè okuta nla mẹta, ati ilè igi titun kan: ki a si ṣe inawo rẹ̀ lati inu ile ọba wa: 5 Pẹlupẹlu ki a si kó ohun èlo wura ati ti fàdaka ile Ọlọrun pada, ti Nebukadnessari ti kó lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si ti ko wá si Babiloni, ki a si ko wọn pada, ki a si mu wọn lọ si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, olukuluku ni ipò rẹ̀, ki a si tò wọn si inu ile Ọlọrun.

Dariusi Pàṣẹ pé Kí Wọ́n Máa Bá Iṣẹ́ Lọ

6 Njẹ nisisiyi Tatnai, bãlẹ oke-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ nyin, awọn ara Afarsaki, ti o wà li oke-odò, ki ẹnyin ki o jina si ibẹ. 7 Ẹ jọwọ́ iṣẹ ile Ọlọrun yi lọwọ, ki balẹ awọn ara Juda, ati awọn àgba awọn ara Juda ki nwọn kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀. 8 Pẹlupẹlu mo paṣẹ li ohun ti ẹnyin o ṣe fun awọn àgba Juda wọnyi, fun kikọ ile Ọlọrun yi: pe, ninu ẹru ọba, li ara owo-odè li oke-odò, ni ki a mã ṣe ináwo fun awọn enia wọnyi li aijafara, ki a máṣe da wọn duro. 9 Ati eyiti nwọn kò le ṣe alaini ẹgbọrọ akọmalu, ati àgbo, pẹlu ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun si Ọlọrun ọrun, alikama, iyọ, ọti-waini pẹlu ororo, gẹgẹ bi ilana awọn alufa ti o wà ni Jerusalemu, ki a mu fun wọn li ojojumọ laiyẹ̀: 10 Ki nwọn ki o le ru ẹbọ olõrun, didùn si Ọlọrun ọrun, ki nwọn ki o si le ma gbadura fun ẹmi ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀. 11 Pẹlupẹlu mo ti paṣẹ pe, ẹnikẹni ti o ba yi ọ̀rọ yi pada, ki a fa igi lulẹ li ara ile rẹ̀, ki a si gbe e duro, ki a fi on na kọ si ori rẹ̀, ki a si sọ ile rẹ̀ di ãtàn nitori eyi. 12 Ki Ọlọrun ẹniti o mu ki orukọ rẹ̀ ma gbe ibẹ, ki o pa gbogbo ọba, ati orilẹ-ède run, ti yio da ọwọ wọn le lati ṣe ayipada, ati lati pa ile Ọlọrun yi run, ti o wà ni Jerusalemu. Emi Dariusi li o ti paṣẹ, ki a mu u ṣẹ li aijafara.

Wọ́n Ya Tẹmpili sí Mímọ́

13 Nigbana ni Tatnai bãlẹ ni ihahin-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ wọn, gẹgẹ bi eyiti Dariusi ọba ti ranṣẹ, bẹ̃ni nwọn ṣe li aijafara. 14 Awọn àgba Juda si kọle, nwọn si ṣe rere nipa iyanju Haggai woli ati Sekariah ọmọ Iddo. Nwọn si kọle, nwọn si pari rẹ̀ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Israeli, ati gẹgẹ bi aṣẹ Kirusi, ati Dariusi ati Artasasta ọba Persia. 15 A si pari ile yi li ọjọ kẹta oṣu Adari, ti iṣe ọdun kẹfa ijọba Dariusi ọba. 16 Awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pẹlu awọn ọmọ ìgbekun ìyoku ṣe ìyasimimọ́ ile Ọlọrun yi pẹlu ayọ̀. 17 Ni iyasimimọ́ ile Ọlọrun yi, ni nwọn si rubọ ọgọrun akọ-malu, igba àgbo, irinwo ọdọ-agutan; ati fun ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli, obukọ mejila gẹgẹ bi iye awọn ẹ̀ya Israeli: 18 Nwọn si fi awọn alufa si gẹgẹ bi ipa wọn ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ipa wọn, fun isin Ọlọrun ni Jerusalemu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose.

Àjọ Ìrékọjá

19 Awọn ọmọ igbekun si ṣe ajọ irekọja li ọjọ kẹrinla oṣu ekini. 20 Nitoriti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ti wẹ̀ ara wọn mọ́ bi ẹnikan, gbogbo wọn li o si mọ́, nwọn si pa ẹran irekọja fun gbogbo awọn ọmọ igbekun, ati fun awọn arakunrin wọn, awọn alufa, ati fun awọn tikara wọn. 21 Awọn ọmọ Israeli ti o ti inu igbekun pada bọ̀, ati gbogbo iru awọn ti o ti ya ara wọn si ọdọ wọn kuro ninu ẽri awọn keferi ilẹ na, lati ma ṣe afẹri Oluwa Ọlọrun Israeli, si jẹ àse irekọja. 22 Nwọn si fi ayọ̀ ṣe ajọ aiwukara li ọjọ meje: nitoriti Oluwa ti mu wọn yọ̀, nitoriti o yi ọkàn ọba Assiria pada si ọdọ wọn, lati mu ọwọ wọn le ninu iṣẹ ile Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.

Esra 7

Ẹsra Dé sí Jerusalẹmu

1 NJẸ lẹhin nkan wọnyi, ni ijọba Artasasta ọba Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah, 2 Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, 3 Ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraiotu, 4 Ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki, 5 Ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olori alufa: 6 Esra yi li o gòke lati Babiloni wá; o si jẹ ayáwọ́-akọwe ninu ofin Mose, ti Oluwa Ọlọrun Israeli fi fun ni: ọba si fun u li ohun gbogbo ti o bère, gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ti wà lara rẹ̀. 7 Ati ninu awọn ọmọ Israeli, ati ninu awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, pẹlu awọn Netinimu si goke wá si Jerusalemu li ọdun keje Artasasta ọba. 8 On si wá si Jerusalemu li oṣu karun, eyi ni ọdun keje ọba. 9 Nitoripe lati ọjọ kini oṣu ekini li o bẹrẹ si igòke lati Babiloni wá, ati li ọjọ ikini oṣu karun li o de Jerusalemu, gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun rẹ̀ ti o wà lara rẹ̀. 10 Nitori Esra ti mura tan li ọkàn rẹ̀ lati ma wá ofin Oluwa, ati lati ṣe e, ati lati ma kọ́ni li ofin ati idajọ ni Israeli.

Àkọsílẹ̀ tí Atasasesi Ọba fún Ẹsra

11 Eyi si ni atunkọ iwe na ti Artasasta ọba fi fun Esra alufa, akọwe, ani akọwe ọ̀rọ ofin Oluwa, ati ti aṣẹ rẹ̀ fun Israeli. 12 Artasasta, ọba awọn ọba, si Esra alufa, akọwe pipé ti ofin Ọlọrun ọrun, alafia: 13 Mo paṣẹ pe, ki gbogbo enia ninu awọn enia Israeli, ati ninu awọn alufa rẹ̀ ati awọn ọmọ Lefi, ninu ijọba mi, ẹniti o ba fẹ nipa ifẹ inu ara wọn lati gòkẹ lọ si Jerusalemu, ki nwọn ma ba ọ lọ. 14 Niwọn bi a ti rán ọ lọ lati iwaju ọba lọ ati ti awọn ìgbimọ rẹ̀ mejeje, lati wadi ọ̀ran ti Juda ati Jerusalemu gẹgẹ bi ofin Ọlọrun rẹ ti mbẹ li ọwọ rẹ; 15 Ati lati ko fàdaka ati wura, ti ọba ati awọn ìgbimọ fi tinutinu fi fun Ọlọrun Israeli, ibugbe ẹniti o wà ni Jerusalemu. 16 Ati gbogbo fàdaka ati wura ti iwọ le ri ni gbogbo igberiko Babiloni, pẹlu ọrẹ atinuwa awọn enia, ati ti awọn alufa, ti iṣe ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun wọn ti o wà ni Jerusalemu. 17 Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu. 18 Ati ohunkohun ti o ba wu ọ, ati awọn arakunrin rẹ lati fi fàdaka ati wura iyokù ṣe, eyini ni ki ẹnyin ki o ṣe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun nyin. 19 Ohun-èlo wọnni ti a fi fun ọ pẹlu fun ìsin ile Ọlọrun rẹ, ni ki iwọ ki o fi lelẹ niwaju Ọlọrun ni Jerusalemu. 20 Ati ohunkohun ti a ba fẹ pẹlu fun ile Ọlọrun rẹ, ti iwọ o ri àye lati nawo rẹ̀, nawo rẹ̀ lati inu ile iṣura ọba wá. 21 Ati emi, ani Artasasta ọba paṣẹ fun gbogbo awọn olutọju iṣura, ti o wà li oke odò pe, ohunkohun ti Esra alufa, ti iṣe akọwe ofin Ọlọrun ọrun yio bère lọwọ nyin, ki a ṣe e li aijafara, 22 Titi de ọgọrun talenti fàdaka, ati de ọgọrun oṣuwọn alikama, ati de ọgọrun bati ọti-waini, ati de ọgọrun bati ororo, ati iyọ laini iye. 23 Ohunkohun ti Ọlọrun ọrun palaṣẹ, ki a fi otitọ ṣe e fun ile Ọlọrun ọrun: ki ibinu ki o má de si ijọba ọba, ati awọn ọmọ rẹ̀. 24 Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin kò ni oyè lati di owo-ori, owo-odè, ati owo-bodè ru gbogbo awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, awọn akọrin, awọn adèna, awọn Netinimu, ati awọn iranṣẹ ninu ile Ọlọrun yi, 25 Ati iwọ, Esra, gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun rẹ ti o wà li ọwọ rẹ, yan awọn oloyè ati onidajọ, ti nwọn o ma da ẹjọ fun gbogbo awọn enia ti o wà li oke-odò, gbogbo iru awọn ti o mọ̀ ofin Ọlọrun rẹ, ki ẹnyin ki o si ma kọ́ awọn ti kò mọ̀ wọn. 26 Ẹnikẹni ti kì o si ṣe ofin Ọlọrun rẹ, ati ofin ọba, ki a mu idajọ ṣe si i lara li aijafara, bi o ṣe si ikú ni, tabi lilé si oko, tabi kiko li ẹrù, tabi si sisọ sinu tubu.

Ẹsra Yin Ọlọrun

27 Olubukun li Oluwa Ọlọrun awọn baba wa, ti o fi nkan bi iru eyi si ọkàn ọba, lati ṣe ogo si ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu: 28 Ti o si nàwọ anu si mi niwaju ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀, ati niwaju gbogbo awọn alagbara ijoye ọba: mo si ri iranlọwọ gbà gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun mi ti o wà lara mi, mo si ko awọn olori awọn enia jọ lati inu Israeli jade, lati ba mi goke lọ.

Esra 8

Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú

1 WỌNYI ni awọn olori ninu awọn baba wọn, eyi ti a kọ sinu iwe itan-idile awọn ti o ba mi goke lati Babiloni wá, ni ijọba Artasasta ọba. 2 Ninu awọn ọmọ Finehasi, Gerṣomu: ninu awọn ọmọ Itamari, Danieli: ninu awọn ọmọ Dafidi, Hattuṣi. 3 Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah, ti awọn ọmọ Paroṣi, Ṣekariah: ati pẹlu rẹ̀ li a ka ãdọjọ ọkunrin nipa iwe itan-idile. 4 Ninu awọn ọmọ Pahat-moabu; Elihoenai ọmọ Serahiah, ati pẹlu rẹ̀, igba ọkunrin. 5 Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah; ọmọ Jahasieli, ati pẹlu rẹ̀, ọdunrun ọkunrin. 6 Ninu awọn ọmọ Adini pẹlu, Ebedi ọmọ Jonatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọta ọkunrin. 7 Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Jeṣaiah ọmọ Ataliah, ati pẹlu rẹ̀, ãdọrin ọkunrin. 8 Ati ninu awọn ọmọ Ṣefatiah; Sebadiah ọmọ Mikaeli, ati pẹlu rẹ̀, ọgọrin ọkunrin. 9 Ninu awọn ọmọ Joabu; Obadiah ọmọ Jahieli ati pẹlu rẹ̀, ogunlugba ọkunrin o din meji. 10 Ati ninu awọn ọmọ Ṣelomiti; ọmọ Josafiah, ati pẹlu rẹ̀, ọgọjọ ọkunrin. 11 Ati ninu awọn ọmọ Bebai; Sekariah, ọmọ Bebai, ati pẹlu rẹ̀, ọkunrin mejidilọgbọn. 12 Ati ninu awọn ọmọ Asgadi; Johanani ọmọ Hakkatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọfa ọkunrin. 13 Ati ninu awọn ọmọ ikẹhin Adonikamu, orukọ awọn ẹniti iṣe wọnyi, Elifeleti, Jeieli, ati Ṣemaiah, ati pẹlu wọn, ọgọta ọkunrin. 14 Ninu awọn ọmọ Bigfai pẹlu; Uttai, ati Sabbudi, ati pẹlu wọn, ãdọrin ọkunrin. 15 Mo si kó wọn jọ pọ li eti odò ti o ṣàn si Ahafa; nibẹ li a si gbe inu agọ li ọjọ mẹta: mo si wò awọn enia rere pẹlu awọn alufa, emi kò si ri ẹnikan ninu awọn ọmọ Lefi nibẹ. 16 Nigbana ni mo ranṣẹ pè Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, ati Elnatani ati Jaribi, ati Elnatani, ati Natani, ati Sekariah, ati Meṣullamu, awọn olori pẹlu Joiaribi, ati Elnatani, enia oloye. 17 Mo si rán wọn ti awọn ti aṣẹ si ọdọ Iddo, olori ni ibi Kasifia, mo si kọ́ wọn li ohun ti nwọn o wi fun Iddo, ati fun awọn arakunrin rẹ̀, awọn Netinimu ni ibi Kasifia, ki nwọn ki o mu awọn iranṣẹ wá si ọdọ wa fun ile Ọlọrun wa. 18 Ati nipa ọwọ rere Ọlọrun wa lara wa, nwọn mu ọkunrin oloye kan fun wa wá, ninu awọn ọmọ Mali, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli; ati Ṣerebiah, pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, mejidilogun. 19 Ati Haṣabiah, ati pẹlu rẹ̀ Jeṣaiah, ninu awọn ọmọ Merari, awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ wọn, ogún; 20 Ninu awọn Netinimu pẹlu, ti Dafidi ati awọn ijoye ti fi fun isin awọn ọmọ Lefi, ogunlugba Netinimu gbogbo wọn li a kọ orukọ wọn. 21 Nigbana ni mo kede àwẹ kan nibẹ lẹba odò Ahafa, ki awa ki o le pọn ara wa loju niwaju Ọlọrun wa, lati ṣafẹri ọ̀na titọ́ fun wa li ọwọ rẹ̀, ati fun ọmọ wẹrẹ wa, ati fun gbogbo ini wa. 22 Nitoripe, oju tì mi lati bère ẹgbẹ ọmọ-ogun li ọwọ ọba, ati ẹlẹṣin, lati ṣọ wa nitori awọn ọta li ọ̀na: awa sa ti sọ fun ọba pe, Ọwọ Ọlọrun wa mbẹ lara awọn ti nṣe afẹri rẹ̀ fun rere; ṣugbọn agbara rẹ̀ ati ibinu rẹ̀ mbẹ lara gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ. 23 Bẹ̃li awa gbàwẹ, ti awa si bẹ̀ Ọlọrun wa nitori eyi: on si gbọ́ ẹ̀bẹ wa. 24 Nigbana ni mo yàn ẹni-mejila si ọ̀tọ ninu awọn olori awọn alufa, Ṣerebiah, Haṣabiah, ati mẹwa ninu awọn arakunrin wọn pẹlu wọn, 25 Mo si wọ̀n fàdaka ati wura fun wọn, ati ohun èlo, ani ọrẹ ti iṣe ti ile Ọlọrun wa, ti ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo Israeli ti o wà nibẹ, ta li ọrẹ: 26 Mo si wọ̀n ãdọtalelẹgbẹta talenti fàdaka le wọn li ọwọ, ati ohun èlo fàdaka, ọgọrun talenti, ati ti wura, ọgọrun talenti, 27 Pẹlu ogun ago wura ẹlẹgbẹgbẹrun dramu, ati ohun èlo meji ti bàba daradara, ti o niye lori bi wura. 28 Mo si wi fun wọn pe, Mimọ́ li ẹnyin si Oluwa; mimọ́ si li ohun èlo wọnyi; ọrẹ atinuwa si Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin ni fàdaka ati wura na. 29 Ẹ ma tọju wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ, titi ẹnyin o fi wọ̀n wọn niwaju awọn olori ninu awọn alufa ati ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori ninu awọn baba Israeli ni Jerusalemu, ninu iyàrá ile Oluwa. 30 Bẹ̃ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu fàdaka ati wura ti a wọ̀n pẹlu ohun-èlo wọnni lati ko wọn wá si Jerusalemu, sinu ile Ọlọrun wa.

Pípadà sí Jerusalẹmu

31 Nigbana ni awa lọ kuro ni odò Ahafa, li ọjọ ekejila oṣu ikini, lati lọ si Jerusalemu: ọwọ Ọlọrun wa si wà lara wa, o si gba wa lọwọ awọn ọta, ati lọwọ iru awọn ti o ba ni ibuba li ọ̀na. 32 Awa si de Jerusalemu, awa si simi nibẹ li ọjọ mẹta. 33 Li ọjọ ẹkẹrin li a wọ̀n fàdaka ati wura ati ohun-èlo wọnni ninu ile Ọlọrun wa si ọwọ Meremoti ọmọ Uriah, alufa, ati pẹlu rẹ̀ ni Eleasari ọmọ Finehasi; ati pẹlu wọn ni Josabadi ọmọ Jeṣua, ati Noadia, ọmọ Binnui, awọn ọmọ Lefi; 34 Nipa iye, ati nipa ìwọn ni gbogbo wọn: a si kọ gbogbo ìwọn na sinu iwe ni igbana. 35 Ọmọ awọn ti a ti ko lọ, awọn ti o ti inu igbekùn pada bọ̀, ru ẹbọ sisun si Ọlọrun Israeli, ẹgbọrọ malu mejila, àgbo mẹrindilọgọrun, ọdọ-agutan mẹtadilọgọrin, ati obukọ mejila fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: gbogbo eyi jẹ ẹbọ sisun si Oluwa. 36 Nwọn si fi aṣẹ ọba fun awọn ijoye ọba, ati fun awọn balẹ ni ihahin odò: nwọn si ràn awọn enia na lọwọ, ati ile Ọlọrun.

Esra 9

Ẹsra gbọ́ pé Àwọn Ọmọ Israẹli ń fẹ́ Àwọn Ọmọbinrin tí wọn kì í ṣe Juu

1 NIGBATI a si ti ṣe nkan wọnyi tan, awọn ijoye wá si ọdọ mi, wipe, Awọn enia Israeli, ati awọn alufa, pẹlu awọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn si ọ̀tọ kuro ninu awọn enia ilẹ wọnni, gẹgẹ bi irira wọn, ti awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Perisi, awọn ara Jebusi, awọn ara Ammoni, awọn ara Moabu, awọn ara Egipti, ati ti awọn ara Amori. 2 Nitoripe nwọn mu awọn ọmọ wọn obinrin fun aya wọn, ati fun awọn ọmọ wọn ọkunrin: tobẹ̃ ti a da iru-ọmọ mimọ́ pọ̀ mọ awọn enia ilẹ wọnni: ọwọ awọn ijoye, ati awọn olori si ni pataki ninu irekọja yi. 3 Nigbati mo si gbọ́ nkan wọnyi, mo fa aṣọ mi ati agbáda mi ya, mo si fà irun ori mi ati ti àgbọn mi tu kuro, mo si joko ni ijaya. 4 Nigbana ni olukuluku awọn ti o warìri si ọ̀rọ Ọlọrun Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ mi, nitori irekọja awọn wọnni ti a ti ko lọ; mo si joko ni ijaya titi di igba ẹbọ aṣalẹ. 5 Ni igba ẹbọ aṣalẹ ni mo si dide kuro ninu ikãnu mi; pẹlu aṣọ ati agbáda mi yiya, mo si wolẹ lori ẽkun mi, mo si nà ọwọ mi si Oluwa Ọlọrun mi. 6 Mo si wipe, Ọlọrun mi, oju tì mi, iṣãju si ṣe mi lati gbe oju mi soke si ọdọ rẹ, Ọlọrun mi, nitoriti ẹ̀ṣẹ wa di pupọ li ori wa, ẹbi wa si tobi titi de awọn ọrun. 7 Lati ọjọ awọn baba wa li awa ti wà ninu ẹbi nla titi di oni; ati nitori ẹ̀ṣẹ wa li a fi awa, awọn ọba wa, ati awọn alufa wa, le awọn ọba ilẹ wọnni lọwọ fun idà, fun igbèkun, ati fun ikogun, ati fun idamu oju, gẹgẹ bi o ti ri li oni oloni. 8 Njẹ nisisiyi fun igba diẹ, li a si fi ore-ọfẹ fun wa lati ọdọ Oluwa Ọlọrun wa wá lati salà, ati lati fi ẽkàn fun wa ni ibi mimọ́ rẹ̀, ki Ọlọrun wa ki o le mu oju wa mọlẹ, ki o si tun wa gbe dide diẹ ninu oko-ẹrú wa. 9 Nitoripe ẹrú li awa iṣe; ṣugbọn Ọlọrun wa kò kọ̀ wa silẹ li oko ẹrú wa, ṣugbọn o ti nawọ́ ãnu rẹ̀ si wa li oju awọn ọba Persia, lati tun mu wa yè, lati gbe ile Ọlọrun wa duro, ati lati tun ahoro rẹ̀ ṣe, ati lati fi odi kan fun wa ni Juda, ati ni Jerusalemu. 10 Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, kili awa o wi lẹhin eyi? nitoriti awa ti kọ̀ aṣẹ rẹ silẹ, 11 Ti iwọ ti pa lati ẹnu awọn woli iranṣẹ rẹ wá, wipe, Ilẹ na ti ẹnyin nlọ igbà nì, ilẹ alaimọ́ ni, fun ẹgbin awọn enia ilẹ na, fun irira wọn, pẹlu ìwa-ẽri ti nwọn fi kun lati ikangun kan de ekeji. 12 Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o máṣe fi ọmọ nyin obinrin fun ọmọ wọn ọkunrin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ọmọ wọn obinrin fun ọmọ nyin ọkunrin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe wá alafia wọn tabi irọra wọn titi lai: ki ẹnyin ki o le ni agbara, ki ẹ si le ma jẹ ire ilẹ na, ki ẹ si le fi i silẹ fun awọn ọmọ nyin ni ini titi lai. 13 Ati lẹhin gbogbo eyi ti o de si wa nitori iṣe buburu wa, ati nitori ẹbi wa nla, nitoripe iwọ Ọlọrun wa ti dá wa si ju bi o ti yẹ lọ fun aiṣedede wa, o si fi iru igbala bi eyi fun wa; 14 Awa iba ha tun ru ofin rẹ? ki awa ki o si ma ba awọn enia irira wọnyi dá ana? iwọ kì o ha binu si wa titi iwọ o fi pa wa run tan, tobẹ̃ ti ẹnikan kò si ni kù, tabi ẹnikan ti o sala? 15 Olododo ni iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli: awa ni iyokù ati asala gẹgẹ bi o ti ri li oni yi: wò o, awa duro niwaju rẹ ninu ẹbi wa, nitoripe awa ki o le duro niwaju rẹ nitori eyi.

Esra 10

Ètò láti fi Òpin sí Igbeyawo láàrin àwọn Juu ati àwọn tí Wọn kì í ṣe Juu

1 NIGBATI Esra ti gba adura, ti o si jẹwọ pẹlu ẹkún ati idojubolẹ niwaju ile Ọlọrun, ijọ enia pupọ kó ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀ lati inu Israeli jade, ati ọkunrin ati obinrin ati ọmọ wẹwẹ: nitori awọn enia na sọkun gidigidi. 2 Ṣekaniah ọmọ Jehieli, lati inu awọn ọmọ Elamu dahùn o si wi fun Esra pe, Awa ti ṣẹ̀ si Ọlọrun wa, ti awa ti mu ajeji obinrin lati inu awọn enia ilẹ na: sibẹ, ireti mbẹ fun Israeli nipa nkan yi. 3 Njẹ nitorina ẹ jẹ ki awa ki o ba Ọlọrun wa da majẹmu, lati kọ̀ gbogbo awọn obinrin na silẹ, ati iru awọn ti nwọn bi gẹgẹ bi ìmọ (Esra) oluwa mi, ati ti awọn ti o wariri si aṣẹ Ọlọrun wa: ki awa ki o si mu u ṣẹ gẹgẹ bi ofin na. 4 Dide! nitori ọran tirẹ li eyi: awa pãpã yio wà pẹlu rẹ, mu ọkàn le ki o si ṣe e. 5 Esra si dide, o si mu awọn olori ninu awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Israeli bura pe, awọn o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Nwọn si bura. 6 Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ. 7 Nwọn si kede ja gbogbo Juda ati Jerusalemu fun gbogbo awọn ọmọ igbèkun, ki nwọn ki o kó ara wọn jọ pọ̀ si Jerusalemu; 8 Ati pe ẹnikẹni ti kò ba wá niwọ̀n ijọ mẹta, gẹgẹ bi ìmọ awọn olori ati awọn agba, gbogbo ini rẹ̀ li a o jẹ, on tikararẹ̀ li a o si yà kuro ninu ijọ awọn enia ti a ti ko lọ. 9 Nitori eyi ni gbogbo awọn enia Juda ati Benjamini ko ara wọn jọ pọ̀ ni ọjọ mẹta si Jerusalemu, li oṣu kẹsan, li ogun ọjọ oṣu; gbogbo awọn enia si joko ni ita ile Ọlọrun ni iwarìri nitori ọ̀ran yi, ati nitori òjo-pupọ. 10 Nigbana ni Esra alufa dide duro, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣẹ̀, ẹnyin ti mu àjeji obinrin ba nyin gbe lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli di pupọ, 11 Njẹ nitorina, ẹ jẹwọ fun Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin, ki ẹnyin ki o si mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ; ki ẹnyin ki o si ya ara nyin kuro ninu awọn enia ilẹ na, ati kuro lọdọ awọn ajeji obinrin. 12 Nigbana ni gbogbo ijọ enia na dahùn, nwọn si wi li ohùn rara pe, Bi iwọ ti wi, bẹ̃ni awa o ṣe. 13 Ṣugbọn awọn enia pọ̀, igba òjo pupọ si ni, awa kò si le duro nita, bẹ̃ni eyi kì iṣe iṣẹ ọjọ kan tabi meji: nitoriti awa ti ṣẹ̀ pupọpupọ ninu ọ̀ran yi. 14 Njẹ ki awọn olori wa ki o duro fun gbogbo ijọ enia, ki a si jẹ ki olukuluku ninu ilu wa ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, ki o wá ni wakati ti a da, ati awọn olori olukuluku ilu pẹlu wọn, ati awọn onidajọ wọn, titi a o fi yi ibinu kikan Ọlọrun wa pada kuro lọdọ wa nitori ọ̀ran yi. 15 Sibẹ Jonatani ọmọ Asaheli, ati Jahasiah ọmọ Tikfa li o dide si eyi, Meṣullamu ati Ṣabbetai, ọmọ Lefi, si ràn wọn lọwọ. 16 Ṣugbọn awọn ọmọ igbekun ṣe bẹ̃. Ati Esra, alufa, pẹlu awọn olori ninu awọn baba, nipa ile baba wọn, ati gbogbo wọn nipa orukọ wọn li a yà si ọ̀tọ, ti nwọn si joko li ọjọ kini oṣu kẹwa, lati wadi ọ̀ran na. 17 Nwọn si ba gbogbo awọn ọkunrin ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe ṣe aṣepari, li ọjọ ekini oṣu ekini. 18 Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah. 19 Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn. 20 Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah. 21 Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah. 22 Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa. 23 Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Josabadi, ati Ṣimei, ati Kelaiah (eyi ni Kelita) Petahiah, Juda, ati Elieseri. 24 Ninu awọn akọrin pẹlu; Eliaṣibu: ati ninu awọn adèna; Ṣallumu, ati Telemi, ati Uri. 25 Pẹlupẹlu ninu Israeli: ninu awọn ọmọ Paroṣi: Ramiah, ati Jesiah, ati Malkiah, ati Miamini, ati Eleasari, ati Malkijah, ati Benaiah. 26 Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Mattaniah, Sekariah, ati Jehieli, ati Abdi, ati Jeremoti, ati Elijah. 27 Ati ninu awọn ọmọ Sattu; Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, ati Jeremoti, ati Sabadi, ati Asisa. 28 Ninu awọn ọmọ Bebai pẹlu; Jehohanani, Hananiah, Sabbai ati Atlai. 29 Ati ninu awọn ọmọ Bani; Meṣullamu, Malluki, ati Adaiah, Jaṣubu, ati Ṣeali ati Ramoti. 30 Ati ninu awọn ọmọ Pahat-moabu Adma ati Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleeli, ati Binnui, ati Manasse. 31 Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Elieseri, Isṣjah, Malkiah, Ṣemaiah, Ṣimeoni, 32 Benjamini, Malluki, ati Ṣemariah. 33 Ninu awọn ọmọ Haṣumu; Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifeleti, Jeremai, Manasse, ati Ṣimei. 34 Ninu awọn ọmọ Bani; Maadai, Amramu ati Ueli. 35 Benaiah, Bedeiah, Kellu, 36 Faniah, Meremoti, Eliaṣibu, 37 Mattaniah, Mattenai ati Jaasau, 38 Ati Bani, ati Binnui, Ṣimei. 39 Ati Ṣelemiah, ati Natani, ati Adaiah, 40 Maknadebai, Saṣai, Ṣarai, 41 Asareeli, ati Ṣelemiah, Ṣemariah. 42 Ṣallumu, Amariah, ati Josefu. 43 Ninu awọn ọmọ Nebo; Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Ṣebina, Jadau, ati Joeli, Benaiah. 44 Gbogbo awọn yi li o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, omiran ninu wọn si ni obinrin nipa ẹniti nwọn li ọmọ.

Nehemiah 1

1 Ọ̀RỌ Nehemiah ọmọ Hakaliah. O si ṣe ninu oṣu Kisleu, ni ogún ọdun, nigba tí mo wà ni Ṣuṣani ãfin.

Ẹ̀dùn Ọkàn Nehemiah fún Jerusalẹmu

2 Ni Hanani, ọkan ninu awọn arakunrin mi, on ati awọn ọkunrin kan lati Juda wá sọdọ mi; mo si bi wọn lere niti awọn ara Juda ti o salà, ti o kù ninu awọn igbekùn, ati niti Jerusalemu. 3 Nwọn si wi fun mi pe, Awọn iyokù, ti a fi silẹ nibẹ ninu awọn igbekùn ni igberiko, mbẹ ninu wahala nla ati ẹ̀gan; odi Jerusalemu si wó lulẹ̀, a si fi ilẹkùn rẹ̀ joná. 4 O si ṣe nigbati mo gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura niwaju Ọlọrun ọrun. 5 Mo si wipe, Emi mbẹ̀bẹ lọdọ rẹ, Oluwa Ọlọrun ọrun, ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ fun awọn ti o fẹ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ: 6 Tẹ́ eti rẹ silẹ̀ nisisiyi, ki o si ṣi oju rẹ, ki iwọ ba le gbọ́ adura iranṣẹ rẹ, ti mo ngbà niwaju rẹ nisisiyi, tọsan toru fun awọn ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ, ti mo si jẹwọ ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ Israeli ti a ti ṣẹ̀ si ọ: ati emi ati ile baba mi ti ṣẹ̀. 7 Awa ti huwa ibàjẹ si ọ, awa kò si pa ofin ati ilana ati idajọ mọ, ti iwọ pa li aṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ. 8 Emi bẹ̀ ọ, ranti ọ̀rọ ti iwọ pa laṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ, wipe, Bi ẹnyin ba ṣẹ̀, emi o tú nyin kakiri sãrin awọn orilẹ-ède: 9 Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada si mi, ti ẹ si pa ofin mi mọ, ti ẹ si ṣe wọn, bi o tilẹ ṣepe ẹnyin ti a ti tì jade wà ni ipẹkun ọrun, emi o ko wọn jọ lati ibẹ wá, emi o si mu wọn wá si ibi ti mo ti yàn lati fi orukọ mi si. 10 Njẹ awọn wọnyi ni awọn iranṣẹ rẹ ati enia rẹ, ti iwọ ti rà pada nipa agbara rẹ nla ati nipa ọwọ agbara rẹ. 11 Oluwa, emi bẹ ọ, tẹ́ eti rẹ silẹ si adura iranṣẹ rẹ, ati si adura awọn iranṣẹ rẹ, ti o fẹ lati bẹ̀ru orukọ rẹ: emi bẹ ọ, ki o si ṣe rere si iranṣẹ rẹ loni, ki o si fun u li ãnu li oju ọkunrin yi. Nitori agbe-ago ọba li emi jẹ.

Nehemiah 2

Nehemiah lọ sí Jerusalẹmu

1 O si ṣe li oṣu Nisani, li ogún ọdun Artasasta ọba, ọti-waini wà niwaju rẹ̀: mo si gbe ọti-waini na, mo si fi fun ọba. Emi kò si ti ifajuro niwaju rẹ̀ rí. 2 Nitorina ni ọba ṣe wi fun mi pe, ẽṣe ti oju rẹ fi faro? iwọ kò sa ṣaisan? eyi kì iṣe ohun miran bikoṣe ibanujẹ. Ẹ̀ru si ba mi gidigidi. 3 Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀? 4 Nigbana ni ọba wi fun mi pe, ẹ̀bẹ kini iwọ fẹ bẹ̀? Bẹ̃ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun. 5 Mo si wi fun ọba pe, Bi o ba wù ọba, ati bi iranṣẹ rẹ ba ri ojurere lọdọ rẹ, ki iwọ le rán mi lọ si Juda, si ilu iboji awọn baba mi, ki emi ki o ba le kọ́ ọ. 6 Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u. 7 Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda; 8 Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi. 9 Nigbana ni mo de ọdọ awọn bãlẹ li oke odo mo si fi iwe ọba fun wọn: Ọba si ti rán awọn olori-ogun ati ẹlẹṣin pẹlu mi. 10 Nigbati Sanballati ara Horoni ati Tobiah iranṣẹ ara Ammoni gbọ́, o bi wọn ni inu gidigidi pe, enia kan wá lati wá ire awọn ọmọ Israeli. 11 Bẹni mo de Jerusalemu, mo si wà nibẹ̀ ni ọjọ mẹta. 12 Mo si dide li oru, emi ati ọkunrin diẹ pẹlu mi: emi kò si sọ fun enia kan ohun ti Ọlọrun mi fi si mi li ọkàn lati ṣe ni Jerusalemu: bẹni kò si ẹranko kan pẹlu mi, bikoṣe ẹranko ti mo gùn. 13 Mo si jade li oru ni ibode afonifoji, ani niwaju kanga Dragoni, ati li ẹnu-ọ̀na ãtàn; mo si wò odi Jerusalemu ti a wó lulẹ̀, ati ẹnu-ọ̀na ti a fi iná sun. 14 Nigbana ni mo lọ si ẹnu-ọ̀na orisun, ati si àbata ọba: ṣugbọn kò si àye fun ẹranko ti mo gun lati kọja. 15 Nigbana ni mo goke lọ li oru lẹba odò, mo si wò odi na: mo si yipada, mo si tún wọ̀ bode afonifoji, mo si yipada. 16 Awọn ijoye kò si mọ̀ ibi ti mo lọ, tabi ohun ti mo ṣe; emi kò ti isọ fun awọn ara Juda tabi fun awọn alufa, tabi fun awọn alagba, tabi fun awọn ijoye; tabi fun awọn iyokù ti o ṣe iṣẹ na. 17 Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Ẹnyin ri ibanujẹ ti awa wà, bi Jerusalemu ti di ahoro, ẹnu-ọ̀na rẹ̀ li a si fi iná sun: ẹ wá, ẹ jẹ ki a mọ odi Jerusalemu, ki a má ba jẹ ẹni-ẹgàn mọ! 18 Nigbana ni mo si sọ fun wọn niti ọwọ Ọlọrun mi, ti o dara li ara mi; ati ọ̀rọ ọba ti o ba mi sọ. Nwọn si wipe, Jẹ ki a dide, ki a si mọ odi! Bẹni nwọn gba ara wọn ni iyanju fun iṣẹ rere yi. 19 Ṣugbọn nigbati Sanballati ara Horoni, ati Tobiah iranṣẹ, ara Ammoni, ati Gesẹmu, ara Arabia, gbọ́, nwọn fi wa rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wa, nwọn si wipe, Kini ẹnyin nṣe yi? ẹnyin o ha ṣọ̀tẹ si ọba bi? 20 Nigbana ni mo da wọn li ohùn mo si wi fun wọn pe, Ọlọrun ọrun, On o ṣe rere fun wa; nitorina awa iranṣẹ rẹ̀ yio dide lati mọ odi: ṣugbọn ẹnyin kò ni ipin tabi ipa tabi ohun iranti ni Jerusalemu.

Nehemiah 3

Títún Ògiri Jerusalẹmu Mọ

1 NIGBANA ni Eliaṣibu olori alufa dide pẹlu awọn alufa arakunrin rẹ̀, nwọn si mọ ẹnu-bode agutan; nwọn sọ ọ di mimọ́, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ duro, titi de ile-iṣọ Mea, ni nwọn sọ di mimọ́ titi de ile-iṣọ Hananeeli. 2 Lọwọkọwọ rẹ̀ ni awọn ọkunrin Jeriko si mọ: lọwọkọwọ wọn ni Sakkuri ọmọ Imri si mọ. 3 Ṣugbọn ẹnu-bode Ẹja ni awọn ọmọ Hasenaa mọ, ẹniti o tẹ́ igi idabu rẹ̀, ti o si gbe ilẹkun rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀. 4 Lọwọkọwọ wọn ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi, tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Sadoku, ọmọ Baana tun ṣe. 5 Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn. 6 Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀. 7 Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò. 8 Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro. 9 Lọwọkọwọ wọn ni Refaiah, ọmọ Huri ijòye idaji Jerusalemu si tun ṣe. 10 Lọwọkọwọ wọn ni Jedaiah, ọmọ Haramafu, si tun ṣe, ani ọkánkan ile rẹ̀. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hattuṣi ọmọ Haṣabaniah si tun ṣe. 11 Malkijah ọmọ Harimu, ati Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu, tun apa keji ṣe, ati ile-iṣọ ileru. 12 Ati lọwọkọwọ rẹ̀ Ṣallumu ọmọ Haloheṣi, ijòye apa kan Jerusalemu, tun ṣe, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀. 13 Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn. 14 Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀. 15 Ṣallumu, ọmọ Kol-hose, ijòye apakan Mispa si tun ẹnu-bode orisun ṣe; o kọ́ ọ, o si bò o, o si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itìkun rẹ̀ ati odi adagun Ṣiloa li ẹ̀ba ọgba ọba, ati titi de atẹ̀gun ti o sọkalẹ lati ile Dafidi lọ. 16 Lẹhin rẹ̀ ni Nehemiah, ọmọ Asbuku, ijòye idaji Bet-huri, tun ṣe titi de ibi ọkánkán iboji Dafidi, ati de adagun ti a ṣe, ati titi de ile awọn alagbara.

Àwọn Ọmọ Lefi tí Wọ́n Ṣiṣẹ́ ní Ibi Odi náà

17 Lẹhin rẹ̀ ni awọn ọmọ Lefi, Rehumu, ọmọ Bani tun ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Haṣabiah ijòye idaji Keila tun ṣe li apa tirẹ̀. 18 Lẹhin rẹ̀ ni awọn arakunrin wọn tun ṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ijoye idaji Keila. 19 Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, ijòye Mispa, tun apa miran ṣe li ọkánkán titọ lọ si ile-ihamọra kọrọ̀ odi. 20 Lẹhin rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sabbai fi itara tun apa miran ṣe, lati igun ogiri titi de ilẹkùn ile Eliaṣibu, olori alufa. 21 Lẹhin rẹ̀ ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi tun apa miran ṣe lati ilẹkùn ile Eliaṣibu titi de ipẹkun ile Eliaṣibu. 22 Lẹhin rẹ̀ ni awọn alufa si tun ṣe, awọn ọkunrin pẹtẹlẹ [Jordani]. 23 Lẹhin wọn ni Benjamini ati Haṣubu tun ṣe li ọkánkán ile wọn. Lẹhin wọn ni Asariah ọmọ Maasiah ọmọ Ananiah tun ṣe lẹba ile rẹ̀. 24 Lẹhin rẹ̀ ni Binnui, ọmọ Henadadi tun apa miran ṣe, lati ile Asariah titi de igun odi, ani titi de kọrọ̀. 25 Palali ọmọ Usai li ọkánkán igun odi, ati ile-iṣọ ti o yọ sode lati ile giga ti ọba wá ti o wà lẹba ile tubu. Lẹhin rẹ̀ ni Padaiah ọmọ Paroṣi. 26 Ṣugbọn awọn Netinimu gbe Ofeli, titi de ọkánkán ẹnu-bode omi niha ila-õrùn ati ile iṣọ ti o yọ sode.

Àwọn Mìíràn tí Wọ́n Tún Ṣiṣẹ́ níbi Odi náà

27 Lẹhin wọn ni awọn ara Tekoa tun apa miran ṣe, li ọkánkán ile-iṣọ nla ti o yọ sode, titi de odi Ofeli. 28 Lati oke ẹnu-bode ẹṣin ni awọn alufa tun apa miran ṣe, olukuluku li ọkánkán ile rẹ̀. 29 Lẹhin wọn ni Sadoku, ọmọ Immeri tun ṣe li ọkánkán ile rẹ̀: lẹhin rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùtọju ẹnubode ila-õrùn tun ṣe. 30 Lẹhin wọn ni Hananiah ọmọ Selamiah tun ṣe, ati Hanuni ọmọ Salafu kẹfa tun apa miran ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah li ọkánkán yàra rẹ̀. 31 Lẹhin rẹ̀ ni Malkiah ọmọ alagbẹdẹ wura tun ṣe, titi de ile awọn Netinimu ati ti awọn oniṣòwo, li ọkánkán ẹnu bode Mifkadi ati yàra òke igun-odi. 32 Ati larin yàra òke igun-odi titi de ẹnu-bode agutan ni awọn alagbẹdẹ wura ati awọn oniṣòwo tun ṣe.

Nehemiah 4

Nehemiah Borí Ìṣòro Tí ó Dojú Kọ Iṣẹ́ Rẹ̀

1 O SI ṣe, nigbati Sanballati gbọ́ pe awa mọ odi na, inu rẹ̀ rú, o si binu pupọ, o si gàn awọn ara Juda. 2 O si sọ niwaju awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ogun Samaria pe, Kini awọn alailera Juda wọnyi nṣe yi? nwọn o ha dá wà fun ara wọn bi? nwọn o ha rubọ? nwọn o ha ṣe aṣepari ni ijọkan? nwọn o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okìti sọji? 3 Tobiah ara Ammoni si wà li eti ọ̀dọ rẹ̀, o si wipe, Eyi ti nwọn mọ gidi, bi kọ̀lọkọlọ ba gùn u, yio tilẹ wo odi okuta wọn lulẹ̀. 4 Gbọ́, Ọlọrun wa; nitoriti awa di ẹni ẹ̀gan: ki iwọ ki o si dà ẹgan wọn si ori ara wọn, ki o si fi wọn fun ikogun ni ilẹ ìgbekun. 5 Ki o má si bo irekọja wọn, má si jẹ ki a wẹ ẹ̀ṣẹ wọn nù kuro niwaju rẹ: nitoriti nwọn bi ọ ni inu niwaju awọn ọ̀mọle, 6 Bẹ̃ni awa mọ odi na: gbogbo odi na ni a si mọ kàn ara wọn titi de ida meji rẹ̀: nitori awọn enia na ni ọkàn lati ṣiṣẹ. 7 O si ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati awọn ara Arabia, ati awọn ara Ammoni, ati awọn ara Aṣdodi gbọ́ pe, a mọ odi Jerusalemu de oke, ati pe a bẹ̀rẹ si tun ibi ti o ya ṣe, inu wọn ru gidigidi. 8 Gbogbo wọn si jọ gbìmọ pọ̀ lati wá iba Jerusalemu jà, ati lati ṣe ika si i. 9 Ṣugbọn awa gba adura wa si Ọlọrun wa, a si yan iṣọ si wọn lọsan ati loru, nitori wọn. 10 Juda si wipe, Agbara awọn ti nru ẹrù dínkù, àlapa pupọ li o wà, tobẹ̃ ti awa kò fi le mọ odi na. 11 Awọn ọta wa si wipe, Nwọn kì yio mọ̀, bẹ̃ni nwọn kì yio ri titi awa o fi de ãrin wọn, ti a o fi pa wọn, ti a o si da iṣẹ na duro. 12 O si ṣe, nigbati awọn ara Juda ti o wà li agbegbe wọn de, nwọn wi fun wa nigba mẹwa pe, Lati ibi gbogbo wá li ẹnyin o pada tọ̀ wa wá. 13 Nitorina ni mo yàn awọn enia si ibi ti o rẹlẹ lẹhin odi, ati si ibi gbangba, mo tilẹ yàn awọn enia gẹgẹ bi idile wọn, pẹlu idà wọn, ọ̀kọ wọn, ati ọrun wọn. 14 Mo si wò, mo si dide, mo si wi fun awọn ìjoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Ẹ máṣe jẹ ki ẹ̀ru wọn bà nyin, ẹ ranti Oluwa ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ki ẹ si jà fun awọn arakunrin nyin, awọn ọmọkunrin nyin, ati awọn ọmọbinrin nyin, awọn aya nyin, ati ile nyin. 15 O si ṣe, nigbati awọn ọta wa gbọ́ pe, o di mimọ̀ fun wa, Ọlọrun ti sọ ìmọ wọn di asan, gbogbo wa si padà si odi na, olukuluku si iṣẹ rẹ̀. 16 O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda. 17 Awọn ti nmọ odi, ati awọn ti nrù ẹrù ati awọn ti o si ndi ẹrù, olukuluku wọn nfi ọwọ rẹ̀ kan ṣe iṣẹ, nwọn si fi ọwọ keji di ohun ìja mu. 18 Olukuluku awọn ọmọ kọ́ idà rẹ̀ li ẹgbẹ rẹ̀, bẹni nwọn si mọ odi. Ẹniti nfọn ipè wà li eti ọdọ mi. 19 Mo si sọ fun awọn ijoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Iṣẹ́ na tobi o si pọ̀, a si ya ara wa lori odi, ẹnikini jina si ẹnikeji. 20 Ni ibi ti ẹnyin ba gbọ́ iro ipè, ki ẹ wá sọdọ wa: Ọlọrun wa yio jà fun wa. 21 Bẹ̃ni awa ṣe iṣẹ na: idaji wọn di ọ̀kọ mu lati kùtukutu owurọ titi irawọ fi yọ. 22 Li àkoko kanna pẹlu ni mo sọ fun awọn enia pe, Jẹ ki olukuluku pẹlu ọmọkunrin rẹ̀ ki o sùn ni Jerusalemu, ki nwọn le jẹ ẹṣọ fun wa li oru, ki nwọn si le ṣe iṣẹ li ọsan. 23 Bẹ̃ni kì iṣe emi, tabi awọn arakunrin mi, tabi awọn ọmọkunrin mi, tabi awọn oluṣọ ti ntọ̀ mi lẹhin, kò si ẹnikan ninu wa ti o bọ́ aṣọ kuro, olukuluku mu ohun ìja rẹ̀ li ọwọ fun ogun.

Nehemiah 5

Níni Àwọn Talaka Lára

1 AWỌN enia ati awọn aya wọn si nkigbe nlanla si awọn ara Juda, arakunrin wọn. 2 Nitori awọn kan wà ti nwọn wipe, Awa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, jẹ pipọ: nitorina awa gba ọkà, awa si jẹ, a si yè. 3 Awọn ẹlomiran wà pẹlu ti nwọn wipe, Awa ti fi oko wa, ọgba-ajara wa, ati ile wa, sọfa, ki awa ki o le rà ọkà ni ìgba ìyan. 4 Ẹlomiran si wipe, Awa ti ṣi owo lati san owo-ori ọba li ori oko wa, ati ọgba-ajara wa. 5 Ati sibẹ ẹran-ara wa si dabi ẹran-ara awọn arakunrin wa, ọmọ wa bi ọmọ wọn: si wo o, awa mu awọn arakunrin wa ati awọn arabinrin wa wá si oko-ẹrú, lati jẹ iranṣẹ, a si ti mu ninu awọn ọmọbinrin wa wá si oko-ẹrú na: awa kò ni agbara lati rà wọn padà: nitori awọn ẹlomiran li o ni oko wa ati ọgbà ajara wa. 6 Emi si binu gidigidi nigbati mo gbọ́ igbe wọn ati ọ̀rọ wọnyi. 7 Mo si ronu ọ̀ran na, mo si ba awọn ijoye ati awọn olori wi, mo si wi fun wọn pe, Ẹnyin ngba ẹdá olukuluku lọwọ arakunrin rẹ̀. Mo si pe apejọ nla tì wọn. 8 Mo si wi fun wọn pe, Awa nipa agbara wa ti rà awọn ara Juda arakunrin wa padà, ti a tà fun awọn keferi; ẹnyin o ha si mu ki a tà awọn arakunrin nyin? tabi ki a ha tà wọn fun wa? Nwọn si dakẹ, nwọn kò ri nkankan dahùn. 9 Mo si wi pẹlu pe, Ohun ti ẹ ṣe kò dara: kò ha yẹ ki ẹ ma rìn ninu ìbẹru Ọlọrun wa, nitori ẹgan awọn keferi ọta wa? 10 Emi pẹlu, ati awọn arakunrin mi, ati awọn ọmọkunrin mi, nyá wọn ni owó ati ọkà, ẹ jẹ ki a pa èlé gbígbà yí tì. 11 Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi. 12 Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi. 13 Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi.

Àìní Ìwà Ìmọ-Tara-Ẹni Nìkan Nehemiah

14 Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ. 15 Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun. 16 Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na. 17 Pẹlupẹlu awọn ti o joko ni tabili mi jẹ ãdọjọ enia ninu awọn ara Juda ati ninu awọn ijoye, laika awọn ti o wá sọdọ wa lati ãrin awọn keferi ti o wà yi wa ka. 18 Njẹ ẹran ti a pese fun mi jẹ malũ kan ati ãyo agutan mẹfa; fun ijọ kan ni a pese adiẹ fun mi pẹlu, ati lẹ̃kan ni ijọ mẹwa onirũru ọti-waini: ṣugbọn fun gbogbo eyi emi kò bere onjẹ bãlẹ, nitori iṣẹ na wiwo lori awọn enia yi. 19 Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti mo ti ṣe fun enia yi.

Nehemiah 6

Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Nehemiah

1 O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;) 2 Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi. 3 Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá? 4 Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna. 5 Nigbana ni Sanballati rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mi bakanna nigba karun ti on ti iwe ṣíṣi lọwọ rẹ̀. 6 Ninu rẹ̀ li a kọ pe, A nrohin lãrin awọn keferi, Gaṣimu si wi pe, iwọ ati awọn ara Juda rò lati ṣọ̀tẹ: nitori idi eyi ni iwọ ṣe mọ odi na, ki iwọ le jẹ ọba wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. 7 Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀. 8 Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni. 9 Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le. 10 Mo si wá si ile Ṣemaiah ọmọ Delaiah ọmọ Mehetabeeli, ti a há mọ, o si wipe, Jẹ ki a pejọ ni ile Ọlọrun ni inu tempili ki a si tì ilẹkùn tempili; nitori nwọn o wá lati pa ọ; nitõtọ, li oru ni nwọn o wá lati pa ọ. 11 Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ. 12 Sa kiyesi i, mo woye pe, Ọlọrun kò rán a, ṣugbọn pe, o nsọ asọtẹlẹ yi si mi: nitori Tobiah ati Sanballati ti bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ. 13 Nitorina li o ṣe bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ, ki emi ba foya, ki emi ṣe bẹ̃, ki emi si ṣẹ̀, ki nwọn le ri ihìn buburu rò, ki nwọn le kẹgàn mi. 14 Ọlọrun mi, rò ti Tobiah ati Sanballati gẹgẹ bi iṣẹ wọn wọnyi, ati ti Noadiah, woli obinrin, ati awọn woli iyokù ti nwọn fẹ mu mi bẹ̀ru,

Ìparí Iṣẹ́ náà

15 Bẹ̃li a pari odi na li ọjọ kẹ̃dọgbọn oṣù Eluli, ni ọjọ mejilelãdọta. 16 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọta wa gbọ́, gbogbo awọn keferi àgbegbe wa si bẹ̀ru, nwọn si rẹ̀wẹsi pupọ li oju ara wọn, nitori nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi. 17 Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, awọn ijòye Juda ran iwe pupọ si Tobiah, iwe Tobiah si de ọdọ wọn. 18 Nitori ọ̀pọlọpọ ni Juda ti ba a mulẹ nitori ti o jẹ ana Sekaniah ọmọ Ara; ọmọ rẹ̀ Johanani si ti fẹ ọmọ Meṣullamu, ọmọ Berekiah. 19 Nwọn sọ̀rọ rere rẹ̀ pẹlu niwaju mi, nwọn si sọ ọ̀rọ mi fun u. Tobiah rán iwe lati da aiya já mi.

Nehemiah 7

1 O SI ṣe, nigbati a mọ odi na tan, ti mo si gbe ilẹkùn ro, ti a si yan awọn oludena ati awọn akọrin, ati awọn ọmọ Lefi, 2 Mo si fun Hanani arakunrin mi, ati Hananiah ijòye ãfin, li aṣẹ lori Jerusalemu: nitori olododo enia li o ṣe, o si bẹ̀ru Ọlọrun jù enia pupọ lọ. 3 Mo si wi fun wọn pe, Ẹ má jẹ ki ilẹkùn odi Jerusalemu ṣi titi õrùn o fi mú; bi nwọn si ti duro, jẹ ki wọn se ilẹkùn, ki nwọn si há wọn, ki nwọn si yan ẹ̀ṣọ ninu awọn ti ngbe Jerusalemu, olukuluku ninu iṣọ rẹ̀, ati olukuluku ninu ile rẹ̀.

Orúkọ Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú

4 Ṣugbọn ilu na gbõrò, o si tobi, awọn enia inu rẹ̀ si kere, a kò si kọ́ ile tan. 5 Ọlọrun mi si fi si mi li ọkàn lati ko awọn ijòye jọ, ati awọn olori, ati awọn enia, ki a le kà wọn nipa idile wọn. Mo si ri iwe idile awọn ti o kọ́ goke wá, mo ri pe, a kọ ọ sinu rẹ̀. 6 Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o gòke wá lati ìgbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ko lọ, ti nwọn tun padà wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀. 7 Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemia, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordikai, Bilṣani, Mispereti, Bigfai, Nehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi; 8 Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbã o le mejilelãdọsan. 9 Awọn ọmọ Ṣefatiah, ojidinirinwo o le mejila. 10 Awọn ọmọ Ara, adọtalelẹgbẹta o le meji. 11 Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun. 12 Awọn ọmọ Elamu, ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta. 13 Awọn ọmọ Sattu, ojilelẹgbẹrin o le marun. 14 Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin. 15 Awọn ọmọ Binnui, ojilelẹgbẹta o le mẹjọ. 16 Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mejidilọgbọn. 17 Awọn ọmọ Asgadi, egbejila o di mejidilọgọrin. 18 Awọn ọmọ Adonikamu ọtalelẹgbẹta o le meje. 19 Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹtadilãdọrin. 20 Awọn ọmọ Adini, ãdọtalelẹgbẹta o le marun. 21 Awọn ọmọ Ateri, ti Hesekiah mejidilọgọrun. 22 Awọn ọmọ Haṣamu, ọrindinirinwo o le mẹjọ. 23 Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹrin. 24 Awọn ọmọ Harifu mejilelãdọfa. 25 Awọn ọmọ Gibioni, marundilọgọrun. 26 Awọn ọkunrin Betlehemu ati Netofa, ọgọsan o le mẹjọ. 27 Awọn ọkunrin Anatoti, mejidilãdoje. 28 Awọn ọkunrin Bet-asmafeti, mejilelogoji. 29 Awọn ọkunrin Kiriat-jearimu, Kefira, ati Beeroti, ọtadilẹgbẹrin o le mẹta, 30 Awọn ọkunrin Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun. 31 Awọn ọkunrin Mikmasi, mejilelọgọfa. 32 Awọn ọkunrin Beteli ati Ai, mẹtalelọgọfa. 33 Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta. 34 Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta. 35 Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo. 36 Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun. 37 Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan. 38 Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin. 39 Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn. 40 Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta. 41 Awọn ọmọ Paṣuri, ẹgbẹfa o le mẹtadiladọta. 42 Awọn ọmọ Harimu ẹgbẹrun o le mẹtadilogun. 43 Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua, ti Kadmieli, ninu ọmọ Hodafa, mẹrinlelãdọrin. 44 Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdọjọ. 45 Awọn oludena: awọn ọmọ Ṣallumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, mejidilogoje. 46 Awọn ọmọ Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Haṣufa, awọn ọmọ Tabbaoti, 47 Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Sia, awọn ọmọ Padoni, 48 Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Salmai, 49 Awọn ọmọ Hanani, awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari, 50 Awọn ọmọ Reaiah, awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda, 51 Awọn ọmọ Gassamu, awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Fasea, 52 Awọn ọmọ Besai, awọn ọmọ Meunimu, awọn ọmọ Nefiṣesimu, 53 Awọn ọmọ Bakbuku, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Harhuri, 54 Awọn ọmọ Basliti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harsa, 55 Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama, 56 Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa. 57 Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Perida, 58 Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli, 59 Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Amoni. 60 Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni jẹ irinwo din mẹjọ. 61 Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli. 62 Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ojilelẹgbẹta ole meji. 63 Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn. 64 Awọn wọnyi wá iwe orukọ wọn ninu awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn nipa idile ṣugbọn a kò ri i: nitorina li a ṣe yà wọn kurò ninu oyè alufa. 65 Bãlẹ na si wi fun wọn pe, ki nwọn máṣe jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi duro pẹlu Urimu, ati Tummimu, 66 Iye gbogbo ijọ jasi ẹgbãmọkanlelogun o le ojidinirinwo. 67 Laikà awọn iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹ-binrin wọn, iye wọn jẹ ẹgbẹtadilẹgbãrin o di ẹtalelọgọta: nwọn si ni ojilugba o le marun akọni ọkunrin ati akọni obinrin. 68 Ẹṣin wọn jẹ ọtadilẹgbẹrin o di mẹrin: ibaka nwọn jẹ ojilugba o le marun: 69 Rakumi jẹ ojilenirinwo o di marun: kẹtẹkẹtẹ jẹ ẹgbẹrinlelọgbọn o di ọgọrin. 70 Omiran ninu awọn olori ninu awọn baba fi nkan si iṣẹ na. Bãlẹ fi ẹgbẹrun dramu wura, ãdọta awokoto, ọrindilẹgbẹta le mẹwa ẹwu alufa sinu iṣura na. 71 Ninu awọn olori ninu awọn baba fi ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbọkanla mina fadaka si iṣura iṣẹ na. 72 Ati eyiti awọn enia iyokù mu wá jẹ ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbã mina fadaka, ati ẹwu alufa mẹtadilãdọrin. 73 Bẹ̃ni awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn oludena, ati awọn akọrin, ati ninu awọn enia, ati awọn Netinimu, ati gbogbo Israeli, ngbe ilu wọn; nigbati oṣu keje si pé, awọn ọmọ Israeli wà ni ilu wọn.

Nehemiah 8

Ẹsira Ka Òfin fún Àwọn Eniyan náà

1 NIGBANA ni gbogbo awọn enia ko ara wọn jọ bi enia kan si ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi; nwọn si sọ fun Esra akọwe lati mu iwe ofin Mose wá, ti Oluwa ti paṣẹ fun Israeli. 2 Esra alufa si mu ofin na wá iwaju ijọ t'ọkunrin t'obinrin, ati gbogbo awọn ti o le fi oye gbọ́, li ọjọ kini oṣu ekeje. 3 O si kà ninu rẹ̀ niwaju ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi lati owurọ titi di idaji ọjọ, niwaju awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati awọn ti o le ye; gbogbo enia si tẹtisilẹ si iwe ofin. 4 Esra akọwe si duro lori aga iduro sọ̀rọ, ti nwọn ṣe nitori eyi na: lẹba ọdọ rẹ̀ ni Mattitiah si duro, ati Ṣema, ati Anaiah, ati Urijah, ati Hilkiah, ati Maaseiah, li ọwọ ọtun rẹ̀; ati li ọwọ òsi rẹ̀ ni Pedaiah, ati Miṣaeli, ati Malkiah, ati Haṣumu, ati Haṣbadana, Sekariah, ati Meṣullamu. 5 Esra si ṣi iwe na li oju gbogbo enia; (nitori on ga jù gbogbo enia) nigbati o si ṣi i, gbogbo enia dide duro: 6 Esra si fi ibukun fun Oluwa Ọlọrun, ti o tobi. Gbogbo enia si dahun pe, Amin, Amin! pẹlu gbigbe ọwọ wọn soke: nwọn si tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn Oluwa ni idojubòlẹ̀. 7 Jeṣua pẹlu ati Bani, ati Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodijah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani, Pelaiah, ati awọn ọmọ Lefi, mu ki ofin ye awọn enia: awọn enia si duro ni ipò wọn. 8 Bẹ̃ni nwọn kà ninu iwe ofin Ọlọrun ketekete, nwọn tumọ rẹ̀, nwọn si mu ki iwe kikà na ye wọn. 9 Ati Nehemiah ti iṣe bãlẹ, ati Esra alufa, akọwe, ati awọn ọmọ Lefi, ti o kọ́ awọn enia wi fun gbogbo enia pe, Ọjọ yi jẹ mimọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin; ẹ má ṣọ̀fọ ki ẹ má si sọkún. Nitori gbogbo awọn enia sọkún, nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ ofin. 10 Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin. 11 Bẹ̃ni awọn ọmọ Lefi mu gbogbo enia dakẹ jẹ, wipe, ẹ dakẹ, nitori mimọ́ ni ọjọ yi; ẹ má si ṣe banujẹ. 12 Gbogbo awọn enia lọ lati jẹ ati lati mu ati lati fi ipin ranṣẹ, ati lati yọ ayọ̀ nla, nitoriti ọ̀rọ ti a sọ fun wọn ye wọn.

Ayẹyẹ Ìpàgọ́

13 Li ọjọ keji awọn olori awọn baba gbogbo awọn enia, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pejọ si ọdọ Esra akọwe, ki o le fi ọ̀rọ ofin ye wọn. 14 Nwọn si ri a kọ sinu iwe-ofin, ti Oluwa ti pa li aṣẹ nipa ọwọ Mose pe, ki awọn ọmọ Israeli gbe inu agọ ni àse oṣu keje: 15 Pe, ki nwọn funrere, ki nwọn kede ni gbogbo ilu wọn, ati ni Jerusalemu, wipe, Ẹ jade lọ si òke, ki ẹ si mu ẹka igi olifi, ẹka igi pine, ati ẹka igi matili (myrtle) imọ ọpẹ, ati ẹka igi ti o tobi, lati ṣe agọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ. 16 Bẹ̃ni awọn enia na jade lọ, nwọn si mu wọn wá, nwọn pa agọ fun ara wọn, olukuluku lori orule ile rẹ̀, ati li àgbala wọn, ati li àgbala ile Ọlọrun, ati ni ita ẹnu-bode omi, ati ni ita ẹnu-bode Efraimu. 17 Gbogbo ijọ enia ninu awọn ti o pada bọ̀ lati oko-ẹrú si pa agọ, nwọn si gbe abẹ awọn agọ na: nitori lati akokò Joṣua ọmọ Nuni wá, titi di ọjọ na awọn ọmọ Israeli kò ṣe bẹ̃. Ayọ̀ nlanla si wà. 18 Esra si kà ninu iwe ofin Ọlọrun li ojojumọ, lati ọjọ kini titi de ọjọ ikẹhin. Nwọn si pa àse na mọ li ọjọ meje, ati lọjọ kẹjọ, nwọn ni apejọ ti o ni ìronu gẹgẹ bi iṣe wọn.

Nehemiah 9

Àwọn Eniyan náà Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn

1 LI ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi, awọn ọmọ Israeli pejọ ninu àwẹ ati aṣọ ọ̀fọ, ati erupẹ lori wọn. 2 Awọn iru-ọmọ Israeli si ya ara wọn kuro ninu awọn ọmọ alejo, nwọn si duro, nwọn jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati aiṣedede awọn baba wọn. 3 Nwọn si dide duro ni ipò wọn, nwọn si fi idamẹrin ọjọ kà ninu iwe ofin Oluwa Ọlọrun wọn; nwọn si fi idamẹrin jẹwọ, nwọn si sìn Oluwa Ọlọrun wọn. 4 Nigbana ni Jeṣua, ati Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani ati Kenani duro lori pẹtẹsì awọn ọmọ Lefi, nwọn si fi ohun rara kigbe si Oluwa Ọlọrun wọn. 5 Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ. 6 Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ. 7 Iwọ ni Oluwa Ọlọrun, ti o ti yan Abramu, ti o si mu u jade lati Uri ti Kaldea wá, iwọ si sọ orukọ rẹ̀ ni Abrahamu; 8 Iwọ si ri pe ọkàn rẹ̀ jẹ olõtọ niwaju rẹ, iwọ si ba a dá majẹmu lati fi ilẹ awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Amori, ati awọn ara Perisi, ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Girgasi fun u, lati fi fun iru-ọmọ rẹ̀, iwọ si ti mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ; nitori olododo ni iwọ: 9 Iwọ si ri ipọnju awọn baba wa ni Egipti, o si gbọ́ igbe wọn lẹba Okun Pupa; 10 O si fi ami, ati iṣẹ-iyanu hàn li ara Farao, ati li ara gbogbo iranṣẹ rẹ̀, ati li ara gbogbo enia ilẹ rẹ̀: nitori iwọ mọ̀ pe, nwọn hu ìwa igberaga si wọn. Iwọ si fi orukọ fun ara rẹ bi ti oni yi. 11 Iwọ si ti pin okun niwaju wọn, nwọn si la arin okun ja li ori ilẹ gbigbẹ; iwọ sọ awọn oninunibini wọn sinu ibú, bi okuta sinu omi lile. 12 Iwọ si fi ọwọ̀n awọ-sanma ṣe amọ̀na wọn li ọsan, ati li oru, ọwọ̀n iná, lati fun wọn ni imọlẹ li ọ̀na ninu eyiti nwọn o rin. 13 Iwọ si sọkalẹ wá si ori òke Sinai, o si bá wọn sọ̀rọ lati ọrun wá, o fun wọn ni idajọ titọ, ofin otitọ, ilana ati ofin rere. 14 Iwọ si mu ọjọ isimi mimọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, o si paṣẹ ẹkọ́, ilana, ati ofin fun wọn, nipa ọwọ Mose iranṣẹ rẹ. 15 O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn. 16 Ṣugbọn awọn ati awọn baba wa hu ìwa igberaga, nwọn si mu ọrùn wọn le, nwọn kò si gba ofin rẹ gbọ́. 17 Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ. 18 Nitõtọ nigbati nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu didà, ti nwọn si wipe, Eyi li Ọlọrun rẹ ti o mu ọ gòke ti Egipti jade wá, nwọn si ṣe imunibinu nla. 19 Ṣugbọn iwọ, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, kò kọ̀ wọn silẹ li aginju, ọwọ̀n kũkũ kò kuro lọdọ wọn lojojumọ lati ṣe amọna wọn, bẹ̃ si li ọwọ̀n iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru li ọ̀na ti nwọn iba rìn. 20 Iwọ fun wọn li ẹmi rere rẹ pẹlu lati kọ́ wọn, iwọ kò si gba manna rẹ kuro li ẹnu wọn, iwọ si fun wọn li omi fun orungbẹ wọn. 21 Nitotọ, ogoji ọdun ni iwọ fi bọ́ wọn li aginju, nwọn kò si ṣe alaini; aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ wọn kò si wú. 22 Pẹlupẹlu iwọ fi ijọba ati orilẹ-ède fun wọn, o si pin wọn si ìha gbogbo, bẹ̃ni nwọn jogun ilẹ Sihoni, ati ilẹ ọba Heṣboni, ati ilẹ Ogu, ọba Baṣani. 23 Awọn ọmọ wọn pẹlu ni iwọ sọ di pipọ bi irawọ ọrun, o si mu wọn wá ilẹ na sipa eyiti o ti leri fun awọn baba wọn pe: ki nwọn lọ sinu rẹ̀ lati gbà a. 24 Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn. 25 Nwọn si gbà ilu alagbara, ati ilẹ ọlọra, nwọn si gbà ilẹ ti o kún fun ohun rere, kanga, ọgba-ajara, ọgba-olifi, ati igi eleso, li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni nwọ́n jẹ, nwọn si yo, nwọ́n sanra, nwọn si ni inu-didùn ninu ore rẹ nla. 26 Ṣugbọn nwọn ṣe alaigbọràn, nwọn si ṣọ̀tẹ si ọ, nwọn si gbe ofin rẹ sọ si ẹ̀hin wọn, nwọn si pa awọn woli rẹ ti nsọ fun wọn lati yipada si ọ, nwọn si ṣe imunibinu nla. 27 Nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ti o pọn wọn loju, ati li akoko ipọnju wọn, nigbati nwọn kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá; ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, iwọ fun wọn li olugbala, ti nwọn gbà wọn kuro lọwọ awọn ọta wọn. 28 Ṣugbọn li ẹhin ti nwọn ni isimi, nwọn si tun ṣe buburu niwaju rẹ: nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, tobẹ̃ ti nwọn jọba li ori wọn: ṣugbọn nigbati nwọn pada, ti nwọn si kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá, ọ̀pọlọpọ ìgba ni iwọ si gbà wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ. 29 Iwọ si jẹri gbè wọn ki iwọ ki o le tun mu wọn wá sinu ofin rẹ, ṣugbọn nwọn hu ìwa igberaga, nwọn kò si fi eti si ofin rẹ, nwọn si ṣẹ̀ si idajọ rẹ (eyiti bi enia ba ṣe on o yè ninu wọn), nwọn si gún èjika, nwọn mu ọrùn wọn le, nwọn kò si fẹ igbọ́. 30 Sibẹ ọ̀pọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suru fun wọn ti o si fi ẹmi rẹ jẹri gbè wọn ninu awọn woli rẹ: sibẹ̀ nwọn kò fi eti silẹ: nitorina ni iwọ ṣe fi wọn le ọwọ awọn enia ilẹ wọnni. 31 Ṣugbọn nitori ãnu rẹ nla iwọ kò run wọn patapata, bẹ̃ni iwọ kò kọ̀ wọn silẹ; nitori iwọ li Ọlọrun olore-ọfẹ ati alãnu. 32 Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, Ọlọrun ti o tobi, ti o li agbara, ti o si li ẹ̀ru, ẹniti npa majẹmu ati ãnu mọ, má jẹ ki gbogbo iyọnu na dabi ohun kekere niwaju rẹ, o de bá wa, awọn ọba wa, awọn ijoye wa, ati awọn alufa wa, ati awọn woli wa, ati awọn baba wa, ati gbogbo awọn enia rẹ lati akoko ọba Assiria wá, titi o fi di oni yi. 33 Sibẹ, iwọ ṣe olododo ninu ohun gbogbo ti o de ba wa, iwọ si ti ṣe otitọ, ṣugbọn awa ti ṣe buburu: 34 Awọn ọba wa, awọn ijoye wa, awọn alufa wa, ati awọn baba wa, kò pa ofin rẹ mọ, bẹ̃ni nwọn kò fi eti si aṣẹ rẹ, ati ẹri rẹ, ti iwọ fi jẹri gbè wọn. 35 Nitori ti nwọn kò sin ọ ninu ijọba wọn, ati ninu ore rẹ nla ti iwọ fi fun wọn, ati ninu ilẹ nla ati ọlọra ti o fi si iwaju wọn, bẹ̃ni nwọn kò pada kuro ninu iṣẹ buburu wọn. 36 Kiyesi i, ẹrú li awa iṣe li oni yi, ati ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa lati ma jẹ eso rẹ̀, ati ire rẹ̀, kiyesi i, awa jẹ ẹrú ninu rẹ̀. 37 Ilẹ na si mu ohun ọ̀pọlọpọ wá fun awọn ọba, ti iwọ ti fi ṣe olori wa nitori ẹ̀ṣẹ wa: nwọn ni aṣẹ lori ara wa pẹlu, ati lori ẹran-nla wa, bi o ti wù wọn, awa si wà ninu wàhala nla. 38 Ati nitori gbogbo eyi awa dá majẹmu ti o daju, a si kọwe rẹ̀; awọn ìjoye wa, awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa si fi èdidi di i.

Nehemiah 10

1 AWỌN ti o fi èdidi di i ni Nehemiah, bãlẹ, ọmọ Hakaliah, ati Sidkijah. 2 Seraiah, Asariah, Jeremiah, 3 Paṣuri, Amariah, Malkijah, 4 Hattuṣi, Ṣebaniah, Malluki, 5 Harimu, Meremoti, Obadiah, 6 Danieli, Ginnetoni, Baruki, 7 Meṣullamu, Abijah, Mijamini, 8 Maaṣiah, Bilgai, Ṣemaiah: alufa li awọn wọnyi. 9 Ati awọn ọmọ Lefi: ati Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui, ọkan ninu awọn ọmọ Henadadi, Kadmieli; 10 Ati awọn arakunrin wọn, Ṣebaniah, Hodijah, Kelita, Pelaiah, Hanani, 11 Mika, Rehobu, Haṣabiah, 12 Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah, 13 Hodijah, Bani, Beninu. 14 Awọn olori awọn enia; Paroṣi, Pahati-moabu, Elamu, Sattu, Bani. 15 Bunni, Asgadi, Bebai, 16 Adonijah, Bigfai, Adini, 17 Ateri, Hiskijah, Assuri, 18 Hodijah, Haṣumu, Besai, 19 Harifi, Anatoti, Nebai, 20 Magpiaṣi, Meṣullamu, Hasiri, 21 Meṣesabeeli, Sadoku, Jaddua, 22 Pelatiah, Hanani, Anaiah, 23 Hoṣea, Hananiah, Haṣubu, 24 Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki, 25 Rehumu, Hasabna, Maaseiah, 26 Ati Ahijah, Hanani, Anani, 27 Malluku, Harimu, Baana. 28 Ati awọn enia iyokù, awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, awọn adèna, awọn akọrin, awọn Netinimu, ati gbogbo awọn ti o ya ara wọn kuro lọdọ awọn enia ilẹ na si ofin Ọlọrun, aya wọn, awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo ẹniti o ni ìmọ ati oye; 29 Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀; 30 Ati pe awa kì yio fi awọn ọmọbinrin wa fun awọn enia ilẹ na, bẹ̃li awa kì yio fẹ ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọ wa. 31 Bi awọn enia ilẹ na ba mu ọjà tabi ohun jijẹ wa li ọjọ isimi lati tà, awa kì yio rà a li ọwọ wọn li ọjọ isimi, tabi li ọjọ mimọ́: awa o si fi ọdun keje silẹ, ati ifi-agbara-gba gbèse. 32 Awa si ṣe ilàna fun ara wa pe, ki olukuluku ma san idamẹta ṣekeli li ọdọdun fun iṣẹ ile Ọlọrun wa. 33 Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa. 34 Awa si dìbo larin awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ati awọn enia, fun ọrẹ igi, lati mu u wá si ile Ọlọrun wa, gẹgẹ bi idile awọn baba wa li akoko ti a yàn li ọdọdun, lati fi daná li ori pẹpẹ Oluwa Ọlọrun wa, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin. 35 Ati lati mu akọso ilẹ wa wá, ati gbogbo akọso eso igi gbogbo, li ọdọdun si ile Oluwa wa: 36 Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa. 37 Ki awa si mu akọso iyẹfun pipò wa wá, ati ọrẹ wa, ati eso oniruru igi wa, ti ọti-waini ati ti ororo fun awọn alufa, si iyẹwu ile Ọlọrun wa, ati idamẹwa ilẹ wa fun awọn ọmọ Lefi, ki awọn ọmọ Lefi ki o le ni idamẹwa ninu gbogbo ilu arọko wa. 38 Alufa ọmọ Aaroni yio si wà pẹlu awọn ọmọ Lefi, nigbati awọn ọmọ Lefi yio gba idamẹwa: awọn ọmọ Lefi yio si mu idamẹwa ti idamẹwa na wá si ile Ọlọrun wa, sinu iyẹwu, sinu ile iṣura. 39 Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Lefi ni yio mu ọrẹ ọkà wá, ti ọti-waini titun, ati ororo, sinu iyẹwu, nibiti ohun èlo ibi mimọ́ gbe wà, ati awọn alufa ti nṣiṣẹ, ati awọn adèna, ati awọn akọrin: awa kì yio si kọ̀ ile Ọlọrun wa silẹ.

Nehemiah 11

Àwọn Eniyan Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

1 AWỌN olori awọn enia si ngbe Jerusalemu: awọn enia iyokù si dìbo lati mu ẹnikan ninu ẹnimẹwa lati ma gbe Jerusalemu, ilu mimọ́, ati mẹsan iyokù lati ma gbe ilu miran. 2 Awọn enia si sure fun gbogbo awọn ọkunrin na ti nwọn yan ara wọn lati gbe Jerusalemu. 3 Wọnyi si ni awọn olori igberiko ti ngbe Jerusalemu, ṣugbọn ninu ilu Juda, olukuluku ngbe inu ilẹ ìni rẹ̀ ninu ilu wọn, eyini ni: awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni. 4 Ati ninu awọn ọmọ Juda ngbe Jerusalemu, ati ninu awọn ọmọ Benjamini. Ninu awọn ọmọ Juda, Ataiah ọmọ Ussiah, ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Mahalaleeli, ninu awọn ọmọ Peresi; 5 Ati Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Kol-hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣiloni. 6 Gbogbo ọmọ Peresi ti ngbe Jerusalemu jẹ adọrinlenirinwo o di meji, alagbara ọkunrin. 7 Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini; Sallu ọmọ Meṣullamu ọmọ Joedi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jesaiah. 8 Ati lẹhin rẹ̀ Gabbai, Sallai, ọrindilẹgbẹrun o le mẹjọ. 9 Joeli ọmọ Sikri si ni alabojuto wọn; ati Juda ọmọ Senua ni igbakeji ni ilu. 10 Ninu awọn alufa: Jedaiah ọmọ Joiaribu, Jakini. 11 Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitibu, ni olori ile Ọlọrun. 12 Awọn arakunrin wọn ti o ṣe iṣẹ ile na jẹ, ẹgbẹrin o le mejilelogun: ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaliah, ọmọ Amsi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah, 13 Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn olori awọn baba, ojilugba o le meji: ati Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahasai, ọmọ Meṣillemoti, ọmọ Immeri, 14 Ati awọn arakunrin wọn, alagbara li ogun, mejidilãdoje: ati olori wọn ni Sabdieli ọmọ ọkan ninu awọn enia nla. 15 Ninu awọn ọmọ Lefi pẹlu: Ṣemaiah, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Bunni; 16 Ati Ṣabbetai ati Josabadi, ninu olori awọn ọmọ Lefi ni alabojuto iṣẹ ode ile Ọlọrun. 17 Ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, ni olori lati bẹ̀rẹ idupẹ ninu adura: ati Bakbukiah ẹnikeji ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati Abda ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni. 18 Gbogbo awọn ọmọ Lefi ninu ilu mimọ́ jẹ ọrinlugba o le mẹrin. 19 Ati awọn adèna, Akkubu, Talmoni, ati awọn arakunrin wọn ti nṣọ ẹnu ọ̀na jẹ mejilelãdọsan. 20 Ati iyokù Israeli, ti awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, wà ni gbogbo ilu Juda, olukuluku ninu ilẹ ìni rẹ̀. 21 Ṣugbọn awọn Netinimu ngbe Ofeli: ati Siha, ati Gispa wà li olori awọn Netinimu. 22 Ati alabojuto awọn ọmọ Lefi ni Jerusalemu ni Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mika. Ninu awọn ọmọ Asafu, awọn akọrin wà lori iṣẹ ile Ọlọrun. 23 Nitori o jẹ aṣẹ ọba nipa ti wọn, pe ki ipin kan ti o yẹ ki o jẹ ti awọn akọrin, li ojojumọ. 24 Ati Petahiah ọmọ Meṣesabeeli ninu awọn ọmọ Serah ọmọ Juda wà li ọwọ ọba ninu gbogbo awọn enia. 25 Ati fun ileto, pẹlu oko wọn, ninu awọn ọmọ Juda ngbe Kirjat-arba, ati ileto rẹ̀, ati ni Diboni, ati ileto rẹ̀, ati ni Jekabseeli, ati ileto rẹ̀, 26 Ati ni Jeṣua, ati ni Molada, ati ni Bet-feleti, 27 Ati ni Hasar-ṣuali, ati ni Beerṣeba, ati ileto rẹ̀, 28 Ati ni Siklagi, ati ni Mekona, ati ninu ileto rẹ̀, 29 Ati ni En-rimmoni, ati ni Sarea, ati Jarmuti, 30 Sanoa, Adullamu, ati ileto wọn, ni Lakiṣi, ati oko rẹ̀, ni Aseka, ati ileto rẹ̀. Nwọn si ngbe lati Beerṣeba titi de afonifoji Hinnomu. 31 Ati awọn ọmọ Benjamini lati Geba de Mikmaṣi, ati Aija, ati Beteli, ati ileto wọn. 32 Ni Anatotu, Nobu, Ananiah, 33 Hasori, Rama, Gittaimu, 34 Hadidi, Seboimu, Neballati, 35 Lodi, ati Ono, afonifoji awọn oniṣọnà, 36 Ati ninu awọn ọmọ Lefi, awọn ìpín Juda si ngbe ilẹ Benjamini.

Nehemiah 12

Orúkọ Àwọn Alufaa ati Àwọn Ọmọ Lefi

1 WỌNYI si ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ti o ba Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli goke lọ, ati Jeṣua: Seraiah Jeremiah, Esra, 2 Amariah, Malluki, Hattuṣi, 3 Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti, 4 Iddo, Ginneto, Abijah, 5 Miamini, Maadiah, Bilga, 6 Ṣemaiah, ati Joiaribu, Jodaiah, 7 Sallu, Amoku, Hilkiah, Jedaiah. Wọnyi li olori awọn alufa, ati ti awọn arakunrin wọn li ọjọ Jeṣua. 8 Ati awọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda, ati Mattaniah, ti o wà lori orin idupẹ, on ati awọn arakunrin rẹ̀. 9 Bakbukiah pẹlu ati Unni, awọn arakunrin wọn, li o kọju si wọn ninu iṣọ.

Àwọn Ìran Jeṣua Olórí Àlùfáà

10 Jeṣua si bi Joiakimu, Joiakimu si bi Eliaṣibu, Eliaṣibu si bi Joiada, 11 Joiada si bi Jonatani, Jonatani si bi Jaddua.

Àwọn Baálé Baálé ní Ìdílé Àwọn Àlùfáà

12 Ninu awọn alufa li ọjọ Joiakimu li awọn olori awọn baba wà: ti Seraiah, Meraiah; ti Jeremiah, Hananiah; 13 Ti Esra, Meṣullamu; ti Amariah, Jehohanani; 14 Ti Meliku, Jonatani; ti Ṣebaniah, Josefu; 15 Ti Harimu, Adna; ti Meraioti, Helkai; 16 Ti Iddo, Sekariah; ti Ginnetoni, Meṣullamu; 17 Ti Abijah, Sikri; ti Miniamini, ti Moadiah, Piltai: 18 Ti Bilga, Sammua; ti Ṣemaiah, Jehonatani; 19 Ati ti Joaribu, Mattenai; ti Jedaiah, Ussi; 20 Ti Sallai, Killai; ti Amoku, Eberi; 21 Ti Hilkiah, Haṣhabiah; ti Jedaiah, Netaneeli; 22 Ninu awọn ọmọ Lefi li ọjọ Eliaṣibu, Joiada, ati Johanani, ati Jaddua, awọn olori awọn baba: li a kọ sinu iwe pẹlu awọn alufa, titi di ijọba Dariusi ara Perṣia. 23 Awọn ọmọ Lefi, olori awọn baba li a kọ sinu iwe itan titi di ọjọ Johanani ọmọ Eliaṣibu.

Ìlànà Iṣẹ́ inú Tẹmpili

24 Awọn olori awọn ọmọ Lefi si ni Haṣabiah, Ṣerebiah, ati Jeṣua ọmọ Kadmieli, pẹlu awọn arakunrin wọn kọju si ara wọn, lati yìn ati lati dupẹ, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi enia Ọlọrun, li ẹgbẹgbẹ ẹṣọ. 25 Mattaniah, ati Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni, Akkubu, jẹ adèna lati ma ṣọ ìloro ẹnu-ọ̀na. 26 Wọnyi wà li ọjọ Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati li ọjọ Nehemiah bãlẹ, ati Esra alufa, ti iṣe akọwe.

Nehemiah Ṣe Ìyàsímímọ́ Odi Ìlú náà

27 Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru. 28 Awọn ọmọ awọn akọrin si ko ara wọn jọ lati pẹ̀tẹlẹ yi Jerusalemu ka, ati lati ileto Netofati wá; 29 Lati ile Gilgali wá pẹlu, ati lati inu ilẹ Geba ati Asmafeti, nitori awọn akọrin ti kọ ileto fun ara wọn yi Jerusalemu kakiri. 30 Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi wẹ̀ ara wọn mọ́, nwọn si wẹ̀ awọn enia mọ́, ati ẹnu-bode, ati odi. 31 Nigbana ni mo mu awọn ijoye Juda wá si ori odi, mo si yàn ẹgbẹ nla meji, ninu awọn ti ndupẹ, ẹgbẹ kan lọ si apa ọtun li ori odi, siha ẹnu-bode àtan. 32 Hoṣaiah si lọ tẹle wọn ati idaji awọn ijoye Juda. 33 Ati Asariah, Esra, ati Meṣullamu, 34 Juda, ati Benjamini, ati Ṣemaiah ati Jeremiah. 35 Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa mu fère lọwọ, Sekariah, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu: 36 Ati awọn arakunrin rẹ̀, Ṣemaiah, ati Asaraeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneeli, ati Juda, Hanani, pẹlu ohun èlo orin Dafidi, enia Ọlọrun, ati Esra akọwe niwaju wọn. 37 Ati ni ẹnu-bode orisun eyi ni ibi ti o kọju si i, nwọn ba àtẹgun ilu Dafidi goke lọ, ni ibi odi ti o goke lọ, ni ikọja ile Dafidi, titi de ẹnu-bode omi, niha ila õrùn. 38 Ati ẹgbẹ keji awọn ti ndupẹ, lọ li odi keji si wọn, ati emi lẹhin wọn, pẹlu idaji awọn enia lori odi, lati ikọja ile iṣọ ileru, titi de odi gbigboro. 39 Nwọn si rekọja oke ẹnu-bode Efraimu wá, ati lati oke ẹnu-bode lailai ati li oke ẹnu-bode ẹja, ati ile-iṣọ Hananieli, ati ile-iṣọ Mea, titi de ẹnu-bode agutan, nwọn si duro li ẹnu-bode tubu. 40 Bayi ni awọn ẹgbẹ meji ti ndupẹ ninu ile Ọlọrun duro, ati emi ati idaji awọn ijoye pẹlu mi. 41 Ati awọn alufa: Eliakimu, Maaseiah, Miniamini Mikaiah, Elioenai, Sekariah, Hananiah mu fère lọwọ; 42 Ati Maaseiah, ati Ṣemaiah, ati Eleasari, ati Ussi, ati Jehohanani, ati Malkijah, ati Elamu, ati Eseri, awọn akọrin kọrin soke, pẹlu Jesrahiah alabojuto. 43 Li ọjọ na pẹlu nwọn ṣe irubọ nla, nwọn si yọ̀ nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ̀ ayọ̀ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ̀ pẹlu, tobẹ̃ ti a si gbọ́ ayọ̀ Jerusalemu li okere reré.

Pípèsè fún Ìjọ́sìn Ní Tẹmpili

44 Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro. 45 Ati awọn akọrin, ati adèna npa ẹṣọ Ọlọrun wọn mọ, ati ẹṣọ iwẹnumọ́, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi; ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀. 46 Nitori li ọjọ Dafidi ati Asafu nigbani awọn olori awọn akọrin wà, ati orin iyìn, ati ọpẹ fun Ọlọrun. 47 Gbogbo Israeli li ọjọ Serubbabeli, ati li ọjọ Nehemiah si fi ipin awọn akọrin, ati ti awọn adèna fun wọn olukuluku ni ipin tirẹ̀ li ojojumọ, nwọn si ya ohun mimọ́ awọn ọmọ Lefi si ọ̀tọ, awọn ọmọ Lefi si yà wọn si ọ̀tọ fun awọn ọmọ Aaroni.

Nehemiah 13

Yíyẹra Kúrò lára Àwọn Àjèjì

1 LI ọjọ na, a kà ninu iwe Mose li eti gbogbo enia, ati ninu rẹ̀ li a ri pe, ki ara Ammoni ati ara Moabu ki o má wá sinu ijọ Ọlọrun lailai; 2 Nitoriti nwọn kò fi onjẹ ati omi ko awọn ọmọ Israeli lọna, ṣugbọn nwọn bẹ̀ Balaamu lọwẹ si wọn, lati fi wọn gegun: ṣugbọn Ọlọrun wa sọ egun na di ibukun. 3 O si ṣe, nigbati nwọn ti gbọ́ ofin na, ni nwọn yà gbogbo awọn ọ̀pọ enia ti o darapọ̀ mọ Israeli kuro.

Àtúnṣe Tí Nehemiah ṣe

4 Ati ṣaju eyi, Eliaṣibu alufa, ti o jẹ alabojuto iyẹwu ile Ọlọrun wa jẹ ana Tobiah. 5 O si ti pèse iyẹwu nla kan fun u, nibiti nwọn ima fi ẹbọ ohun jijẹ, turari, ati ohun èlo, ati idamẹwa agbado, ọti-waini titun, ati ororo si nigba atijọ, eyi ti a pa li aṣẹ lati fi fun awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna: ati ẹbọ ọrẹ awọn alufa. 6 Ṣugbọn ni gbogbo àkoko yi, emi kò si ni Jerusalemu: nitori li ọdun kejilelọgbọn ti Artasasta ọba Babiloni, mo wá si ọdọ ọba, ati li opin ọjọ wọnni, mo gba àye lati ọdọ ọba. 7 Mo si wá si Jerusalemu, mo si mọ̀ buburu ti Eliaṣibu ṣe nitori Tobiah, ni pipèse iyẹwu fun u, ninu àgbala ile Ọlọrun. 8 O si bà mi ninu jẹ gidigidi, nitorina mo da gbogbo ohun èlo Tobiah jade kuro ninu iyẹwu na. 9 Nigbana ni mo paṣẹ, nwọn si wẹ̀ iyẹwu na mọ: si ibẹ ni mo si tun mu ohun èlo ile Ọlọrun wá, pẹlu ẹbọ ohun jijẹ ati turari. 10 Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀. 11 Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn. 12 Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura. 13 Mo si yàn olupamọ si ile iṣura, Ṣelemiah alufa ati Sadoku akọwẹ, ati ninu awọn ọmọ Lefi, Pedaiah: ati lọwọkọwọ wọn ni Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah: nitoriti a kà wọn si olõtọ, iṣẹ́ wọn si ni lati ma pin fun awọn arakunrin wọn. 14 Ranti mi, Ọlọrun mi, nitori eyi, ki o má si nu iṣẹ rere ti mo ti ṣe fun ile Ọlọrun mi, nu kuro, ati fun akiyesi rẹ̀. 15 Li ọjọ wọnni ni mo ri awọn kan ti nfunti ni Juda li ọjọ isimi, awọn ti nmu iti ọka wale, ti ndi ẹrù rù kẹtẹkẹtẹ; ti ọti-waini, pẹlu eso àjara, ati eso ọ̀pọtọ, ati gbogbo oniruru ẹrù ti nwọn nmu wá si Jerusalemu li ọjọ isimi: mo si jẹri gbè wọn li ọjọ ti nwọn ntà ohun jijẹ. 16 Awọn ara Tire ngbe ibẹ pẹlu, ti nwọn mu ẹja, ati oniruru ohun èlo wá, nwọn si ntà li ọjọ isimi fun awọn ọmọ Juda, ati ni Jerusalemu. 17 Nigbana ni mo ba awọn ijoye Juda jà, mo si wi fun wọn pe, ohun buburu kili ẹnyin nṣe yi, ti ẹ si mba ọjọ isimi jẹ. 18 Bayi ha kọ́ awọn baba nyin ṣe, Ọlọrun kò ha mu ki gbogbo ibi yi wá sori wa, ati sori ilu yi? ṣugbọn ẹnyin mu ibinu ti o pọ̀ju wá sori Israeli nipa biba ọjọ isimi jẹ. 19 O si ṣe, nigbati ẹnu-bode Jerusalemu bẹ̀rẹ si iṣu okunkun ṣaju ọjọ isimi, mo paṣẹ pe, ki a tì ilẹkun, ki ẹnikẹni má ṣi i titi di ẹhin ọjọ isimi, ninu awọn ọmọkunrin mi ni mo fi si ẹnu-bode, ki a má ba mu ẹrù wọle wá li ọjọ isimi. 20 Bẹ̃ni awọn oniṣòwo ati awọn ti ntà oniruru nkan sùn lẹhin odi Jerusalemu li ẹrinkan tabi ẹrinmeji. 21 Nigbana ni mo jẹri gbè wọn, mo si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sùn lẹhin odi, bi ẹnyin ba tun ṣe bẹ̃, emi o fọwọ bà nyin. Lati àkoko na lọ ni nwọn kò si wá lọjọ isimi mọ. 22 Mo si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ya ara wọn si mimọ, ki nwọn si wa ṣọ ẹnu-bode lati pa ọjọ isimi mọ. Ranti mi Ọlọrun mi nitori eyi pẹlu, ki o si da mi si gẹgẹ bi ọ̀pọ ãnu rẹ. 23 Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, mo ri ara Juda ti mba obinrin awọn ara Aṣdodi, Ammoni, ati ti Moabu gbe: 24 Awọn ọmọ wọn si nsọ apakan ède Aṣdodi, nwọn kò si le sọ̀rọ li ède awọn ara Juda, ṣugbọn gẹgẹ bi ède olukuluku. 25 Mo si ba wọn jà, mo gàn wọn, mo lù ninu wọn, mo tu irun wọn, mo mu wọn fi Ọlọrun bura pe, Ẹnyin kì yio fi ọmọbinrin nyin fun ọmọkunrin nwọn, tabi ọmọbinrin nwọn fun ọmọkunrin nyin tabi fun ara nyin. 26 Solomoni ọba Israeli kò ha dẹṣẹ nipa nkan wọnyi? Bẹ̃ni li ãrin orilẹ-ède pupọ, kò si ọba kan bi on ti Ọlọrun rẹ̀ fẹràn; Ọlọrun si fi jẹ ọba li ori gbogbo Israeli, bẹ̃ni on li awọn àjeji obinrin mu ki o ṣẹ̀. 27 Njẹ ki awa ha gbọ́ ti nyin, lati ṣe gbogbo buburu nla yi, lati ṣẹ̀ si Ọlọrun sa, ni gbigbe awọn àjeji obinrin ni iyawo? 28 Ati ọkan ninu awọn ọmọ Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olori alufa, jẹ ana Sanballati, ara Horoni, nitori na mo le e kuro lọdọ mi. 29 Ranti wọn, Ọlọrun mi, nitoriti nwọn ti ba oyè alufa jẹ, pẹlu majẹmu oyè-alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi. 30 Bayi ni mo wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo awọn alejo, mo si yan ẹ̀ṣọ awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, olukuluku ninu iṣẹ tirẹ̀. 31 Ati fun ẹ̀bun igi li àkoko ti a yàn, ati fun akọso. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere.

Esteri 1

Ayaba Faṣiti Rí Ahaswerusi Ọba Fín

1 O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:) 2 Li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi, ọba, joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni Ṣuṣani, ãfin. 3 Li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o sè àse kan fun gbogbo awọn ijoye ati awọn iranṣẹ rẹ̀; awọn balogun Persia ati Media, awọn ọlọla, ati awọn olori ìgberiko wọnni wà niwaju rẹ̀: 4 Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o logo, ati ọṣọ iyebiye ọlanla rẹ̀ han lọjọ pipọ̀, ani li ọgọsan ọjọ. 5 Nigbati ọjọ wọnyi si pari, ọba sè àse kan li ọjọ meje fun gbogbo awọn enia ti a ri ni Ṣuṣani ãfin, ati àgba ati ewe ni agbala ọgba ãfin ọba. 6 Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́. 7 Ninu ago wura li a si nfun wọn mu, (awọn ohun elo na si yatọ si ara wọn) ati ọti-waini ọba li ọ̀pọlọpọ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to. 8 Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku. 9 Faṣti ayaba sè àse pẹlu fun gbogbo awọn obinrin ni ile ọba ti iṣe ti Ahaswerusi. 10 Li ọjọ keje, nigbati ọti-waini mu inu ọba dùn, o paṣẹ fun Mehumani, Bista, Harbona, Bigta ati Abagta, Ṣetari ati Karkasi, awọn iwẹfa meje ti njiṣẹ niwaju Ahaswerusi ọba. 11 Lati mu Faṣti, ayaba wá siwaju ọba, ti on ti ade ọba, lati fi ẹwà rẹ̀ hàn awọn enia, ati awọn ijoye: nitori arẹwà obinrin ni. 12 Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si gbiná ninu rẹ̀. 13 Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ: 14 Awọn ti o sunmọ ọ ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye Persia ati Media mejeje, ti nri oju ọba, ti nwọn si joko ni ipò ikini ni ijọba). 15 Pe, gẹgẹ bi ofin, Kini ki a ṣe si Faṣti ayaba, nitoriti on kò ṣe bi Ahaswerusi ọba ti paṣẹ fun u, lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀ wá? 16 Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba. 17 Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá. 18 Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide. 19 Bi o ba dara loju ọba, ki aṣẹ ọba ki o ti ọdọ rẹ̀ lọ, ki a si kọ ọ pẹlu awọn ofin Persia ati Media, ki a má ṣe le pa a dà, pe, ki Faṣti ki o máṣe wá siwaju Ahaswerusi ọba mọ, ki ọba ki o si fi oyè ayaba rẹ̀ fun ẹgbẹ rẹ̀ ti o san jù u lọ. 20 Ati nigbati a ba si kede aṣẹ ọba ti on o pa yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, (nitori on sa pọ̀) nigbana ni gbogbo awọn obinrin yio ma bọ̀wọ fun ọkọ wọn, ati àgba ati ewe. 21 Ọ̀rọ na si dara loju ọba ati awọn ijoye; ọba si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Memukani: 22 Nitori on ran ìwe si gbogbo ìgberiko ọba, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède rẹ̀, ki olukulùku ọkunrin ki o le ṣe olori ni ile tirẹ̀, ati ki a le kede rẹ̀ gẹgẹ bi ède enia rẹ̀.

Esteri 2

Ẹsteri Di Ayaba

1 LẸHIN nkan wọnyi, nigbati ibinu Ahaswerusi ọba wa tuka, o ranti Faṣti, ati ohun ti o ti ṣe, ati aṣẹ ti a ti pa nitori rẹ̀. 2 Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba, ti nṣe iranṣẹ fun u, wi pe, jẹ ki a wá awọn wundia ti o li ẹwà fun ọba. 3 Ki ọba ki o si yàn olori ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣà awọn wundia ti o li ẹwà jọ wá si Ṣuṣani ãfin, si ile awọn obinrin, si ọdọ Hegai, ìwẹfa ọba olutọju awọn obinrin; ki a si fi elo ìwẹnumọ́ wọn fun wọn: 4 Ki wundia na ti o ba wù ọba ki o jẹ ayaba ni ipò Faṣti. Nkan na si dara loju ọba, o si ṣe bẹ̃. 5 Ọkunrin ara Juda kan wà ni Ṣuṣani ãfin, orukọ ẹniti ijẹ Mordekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣemei, ọmọ Kisi, ara Benjamini. 6 Ẹniti a ti mu lọ lati Jerusalemu pẹlu ìgbekun ti a kó lọ pẹlu Jekoniah, ọba Juda, ti Nebukadnessari, ọba Babeli ti kó lọ. 7 On li o si tọ́ Hadassa dagba, eyini ni Esteri, ọmọbinrin arakunrin baba rẹ̀: nitori kò ni baba, bẹ̃ni kò si ni iya, wundia na si li ẹwà, o si dara lati wò; ẹniti, nigbati baba ati iya rẹ̀ ti kú tan, Mordekai mu u ṣe ọmọbinrin ontikalarẹ̀, 8 O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin. 9 Wundia na si wù u, o si ri ojurere gbà lọdọ rẹ̀; o si yara fi elo ìwẹnumọ́ rẹ̀ fun u, ati ipin onjẹ ti o jẹ tirẹ̀, ati obinrin meje ti a yàn fun u lati ile ọba wá: on si ṣi i lọ ati awọn wundia rẹ̀ si ibi ti o dara jù ni ile awọn obinrin. 10 Esteri kò ti ifi awọn enia rẹ̀, tabi awọn ibatan rẹ̀ hàn; nitori Mordekai paṣẹ fun u ki o máṣe fi hàn. 11 Mordekai a si ma rìn lojojumọ niwaju àgbala ile awọn obinrin, lati mọ̀ alafia Esteri, ati bi yio ti ri fun u. 12 Njẹ nigbati o kan olukuluku wundia lati wọ̀ ile tọ̀ Ahaswerusi ọba lọ, lẹhin igbati on ba ti gbe oṣù mejila, gẹgẹ bi iṣe awọn obinrin, (nitori bayi ni ọjọ ìwẹnumọ́ wọn pari, oṣù mẹfa ni nwọn fi ikùn òroro ojiá, ati oṣù mẹfa òroro olõrùn didùn, ati pẹlu ohun elo ìwẹnumọ́ awọn obinrin): 13 Bayi ni wundia na iwá si ọdọ ọba; ohunkohun ti o ba bère li a si ifi fun u lati ba a lọ, lati ile awọn obinrin lọ si ile ọba. 14 Li aṣãlẹ on a lọ, ni õrọ ijọ keji on a si pada si ile keji ti awọn obinrin, si ọwọ Ṣaaṣgasi, ìwẹfa, ọba, ti nṣe olutọju awọn obinrin, on kò si gbọdọ wọle tọ̀ ọba wá mọ, bikoṣepe inu ọba ba dùn si i, ti a ba si pè e li orukọ. 15 Njẹ nigbati o kan Esteri, ọmọ Abihaili, arakunrin Mordekai, ẹniti o mu u ṣe ọmọ ara rẹ̀, lati wọle tọ̀ ọba lọ, on kò bère ohunkohun, bikoṣe ohun ti Hegai, ìwẹfa ọba, olutọju awọn obinrin paṣẹ. Esteri si ri ojurere lọdọ gbogbo ẹniti nwò o. 16 Bẹ̃li a mu Esteri wá si ọdọ Ahaswerusi ọba, sinu ile ọba, li oṣù kẹwa, ti iṣe oṣù Tibeti, li ọdun keje ijọba rẹ̀. 17 Ọba si fẹràn Esteri jù gbogbo awọn obinrin lọ, on si ri ore-ọfẹ ati ojurere lọdọ rẹ̀ jù gbogbo awọn wundia na lọ; tobẹ̃ ti o fi gbe ade ọba kà a li ori, o si fi i ṣe ayaba ni ipò Faṣti. 18 Ọba si sè àse nla kan fun gbogbo awọn olori rẹ̀, ati awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ani àse ti Esteri; o si fi isimi fun awọn ìgberiko rẹ̀, o si ṣe itọrẹ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to.

Modekai Yọ Ọba ninu Ewu

19 Nigbati a si kó awọn wundia na jọ li ẹrinkeji, nigbana ni Mordekai joko li ẹnu ọ̀na ile ọba. 20 Esteri kò ti ifi awọn ibatan, tabi awọn enia rẹ̀ hàn titi disisiyi bi Mordekai ti paṣẹ fun u: nitori Esteri npa ofin Mordekai mọ́, bi igba ti o wà li abẹ itọ́ rẹ̀. 21 Li ọjọ wọnni, nigbati Mordekai njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba, meji ninu awọn iwẹfa ọba, Bigtani ati Tereṣi, ninu awọn ti nṣọ iloro, nwọn binu, nwọn si nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba. 22 Nkan na si di mimọ̀ fun Mordekai, o si sọ fun Esteri ayaba; Esteri si fi ọ̀ran na hàn ọba li orukọ Mordekai. 23 Nigbati nwọn si wadi ọ̀ran na, nwọn ri idi rẹ̀; nitorina a so awọn mejeji rọ̀ sori igi; a si kọ ọ sinu iwé-iranti niwaju ọba.

Esteri 3

Hamani Dìtẹ̀ láti Pa Àwọn Juu Run

1 LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀. 2 Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u. 3 Nigbana ni awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, wi fun Mordekai pe, ẽṣe ti iwọ fi nré ofin ọba kọja? 4 O si ṣe, nigbati nwọn wi fun u lojojumọ, ti on kò si gbọ́ ti wọn, nwọn sọ fun Hamani, lati wò bi ọ̀ran Mordekai yio ti le ri: nitori on ti wi fun wọn pe, enia Juda ni on. 5 Nigbati Hamani si ri pe, Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò wolẹ fun on, nigbana ni Hamani kún fun ibinu. 6 O si jẹ abùku loju rẹ̀ lati gbe ọwọ le Mordekai nikan; nitori nwọn ti fi awọn enia Mordekai hàn a: nitorina gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ijọba Ahaswerusi, ni Hamani wá ọ̀na lati parun, ani awọn enia Mordekai. 7 Li oṣù kini, eyinì ni oṣù Nisani, li ọdun kejila ijọba Ahaswerusi, nwọn da purimu, eyinì ni, ìbo, niwaju Hamani, lati ọjọ de ọjọ, ati lati oṣù de oṣù lọ ide oṣù kejila, eyinì ni oṣù Adari. 8 Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si. 9 Bi o ba wù ọba, jẹ ki a kọwe rẹ̀ pe, ki a run wọn: emi o si wọ̀n ẹgbãrun talenti fadaka fun awọn ti a fi iṣẹ na rán, ki nwọn ki o le mu u wá sinu ile iṣura ọba. 10 Ọba si bọ́ oruka rẹ̀ kuro li ọwọ rẹ̀, o si fi fun Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi, ọta awọn Ju. 11 Ọba si wi fun Hamani pe, a fi fadaka na bùn ọ, ati awọn enia na pẹlu, lati fi wọn ṣe bi o ti dara loju rẹ. 12 Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀. 13 A si fi iwe na rán awọn òjiṣẹ si gbogbo ìgberiko ọba, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo enia Juda, ati ọ̀dọ ati arugbo, awọn ọmọde, ati awọn obinrin ki o ṣegbe ni ọjọ kan, ani li ọjọ kẹtala, oṣù kejila, ti iṣe oṣù Adari, ati lati kó ohun iní wọn fun ijẹ. 14 Ọ̀ran iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo igberiko, lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki nwọn ki o le mura de ọjọ na. 15 Awọn ojiṣẹ na jade lọ, nwọn si yara, nitori aṣẹ ọba ni, a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani ãfin. Ati ọba ati Hamani joko lati mu ọti; ṣugbọn ilu Ṣuṣani dãmu.

Esteri 4

Mordekai Wá Ìrànlọ́wọ́ Ẹsteri

1 Nigbati Mordekai mọ̀ gbogbo ohun ti a ṣe, Mordekai fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ-ọ̀fọ on ẽru bò ara, o si jade lọ si ãrin ilu na, o si sọkun kikan ati kikoro. 2 O tilẹ wá siwaju ẹnu-ọna ile ọba: nitori kò si ẹnikan ti o fi aṣọ-ọfọ si ara ti o gbọdọ wọ̀ ẹnu-ọ̀na ile ọba. 3 Ati ni gbogbo ìgberiko, nibiti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, ọ̀fọ nla ba gbogbo awọn Ju; ati ãwẹ, ati ẹkún, ati ipohùnrere; ọ̀pọlọpọ li o si dubulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ninu ẽru. 4 Bẹ̃li awọn iranṣẹbinrin Esteri ati awọn ìwẹfa rẹ̀ wá, nwọn si sọ fun u. Nigbana ni inu ayaba bajẹ gidigidi; o si fi aṣọ ranṣẹ lati fi wọ̀ Mordekai, ati lati mu aṣọ-ọ̀fọ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ṣugbọn on kò gbà a. 5 Nigbana ni Esteri pè Hataki, ọkan ninu awọn ìwẹfa ọba, ẹniti o ti yàn lati duro niwaju rẹ̀, o si rán a si Mordekai lati mọ̀ ohun ti o ṣe, ati nitori kini? 6 Bẹ̃ni Hataki jade tọ̀ Mordekai lọ si ita ilu niwaju ẹnu-ọ̀na ile ọba. 7 Mordekai si sọ ohun gbogbo ti o ri to fun u, ati ti iye owo fadaka ti Hamani ti ṣe ileri lati san si ile iṣura ọba, nitori awọn Ju, lati pa wọn run. 8 Ati pẹlu, o fi iwe aṣẹ na pãpã, ti a pa ni Ṣuṣani lati pa awọn Ju run, le e lọwọ, lati fi hàn Esteri, ati lati sọ fun u, ati lati paṣẹ fun u ki on ki o wọle tọ̀ ọba lọ, lati bẹ̀bẹ lọwọ rẹ̀, ati lati bẹ̀bẹ niwaju rẹ̀, nitori awọn enia rẹ̀. 9 Hataki si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ Mordekai fun Esteri. 10 Esteri si tun sọ fun Hataki, o si rán a si Mordekai. 11 Pe, gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ati awọn enia ìgberiko ọba li o mọ̀ pe, ẹnikẹni ibaṣe ọkunrin tabi obinrin, ti o ba tọ̀ ọba wá sinu àgbala ti inu, ti a kò ba pè, ofin rẹ̀ kan ni, ki a pa a, bikoṣe iru ẹniti ọba ba nà ọpá alade wura si, ki on ki o le yè: ṣugbọn a kò ti ipè mi lati wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ lati ìwọn ọgbọn ọjọ yi wá. 12 Nwọn si sọ ọ̀rọ Esteri fun Mordekai. 13 Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ. 14 Nitori bi iwọ ba pa ẹnu rẹ mọ́ patapata li akokò yi, nigbana ni iranlọwọ ati igbala awọn Ju yio dide lati ibomiran wá; ṣugbọn iwọ ati ile baba rẹ li a o parun: tali o si mọ̀ bi nitori iru akokò bayi ni iwọ ṣe de ijọba? 15 Nigbana ni Esteri rán wọn lọ ifi èsi yi fun Mordekai pe, 16 Lọ, pè awọn Ju ti a le ri ni Ṣuṣani jọ, ki ẹnyin si ma gbãwẹ, fun mi, ki ẹnyin ki o máṣe jẹun, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ni ijọ mẹta t'ọsan t'oru: emi pẹlu ati awọn iranṣẹbinrin mi yio gbãwẹ bẹ̃ gẹgẹ; bẹ̃li emi o si wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ, ti o lòdi si ofin; bi mo ba ṣègbe, mo ṣègbe. 17 Bẹ̃ni Mordekai ba ọ̀na rẹ̀ lọ, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Esteri ti paṣẹ fun u.

Esteri 5

Ẹsteri Pe Ọba ati Hamani sí Àsè

1 O si ṣe li ọjọ kẹta, ni Esteri wọ̀ aṣọ ayaba rẹ̀, o si duro ni àgbala ile ọba ti o wà ninu, lọgangan ile ọba: ọba si joko lori ìtẹ ijọba rẹ̀ ni ile ọba, ti o kọjusi ẹnu-ọ̀na ile na. 2 O si ṣe nigbati ọba ri ti Esteri ayaba duro ni àgbala, on si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀: ọba si nà ọ̀pá alade wura ti o wà lọwọ rẹ̀ si Esteri. Esteri si sunmọ ọ, o si fi ọwọ kàn ori ọpá alade na. 3 Nigbana ni ọba bi i pe, kini iwọ nfẹ́, Esteri ayaba? ati kini ẹ̀bẹ rẹ̀? ani de idajì ijọba li a o si fi fun ọ. 4 Esteri si dahùn pe, bi o ba dara loju ọba, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá loni si àse mi, ti mo ti mura silẹ fun u. 5 Nigbana ni ọba wi pe, ẹ mu ki Hamani ki o yara, ki on ki o le ṣe bi Esteri ti wi. Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá si àse na ti Esteri ti sè silẹ. 6 Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e. 7 Nigbana ni Esteri dahùn, o si wi pe, ẹ̀bẹ mi ati ibère mi ni pe, 8 Bi mo ba ri ore-ọfẹ loju ọba, bi o ba si wù ọba lati fi ohun ti emi ntọrọ fun mi, ati lati ṣe ohun ti emi mbère fun mi, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá si àse ti emi o si tun sè fun wọn, emi o si ṣe li ọla bi ọba ti wi.

Hamani Ṣe Ètò láti Pa Modekai

9 Nigbana ni Hamani jade lọ li ọjọ na tayọ̀tayọ̀, ati pẹlu inu didùn: ṣugbọn nigbati Hamani ri Mordekai li ẹnu ọ̀na ile ọba pe, kò dide duro, bẹ̃ni kò pa ara rẹ̀ da fun on, Hamani kún fun ibinu si Mordekai. 10 Ṣugbọn Hamani kó ara rẹ̀ ni ijanu: nigbati o si de ile, o ranṣẹ lọ ipè awọn ọrẹ rẹ̀, ati Sereṣi aya rẹ̀. 11 Hamani si ròhin ogo ọrọ̀ rẹ̀, ati ọ̀pọlọpọ awọn ọmọ rẹ̀, ati ninu ohun gbogbo ti ọba fi gbe e ga, ati bi o ti gbe on ga jù awọn ijoye, ati awọn ọmọ-ọdọ ọba lọ. 12 Hamani si wi pẹlu pe, ani Esteri ayaba kò mu ki ẹnikẹni ki o ba ọba wá si ibi àse ti o ti sè bikoṣe emi nikan; li ọla ẹ̀wẹ li a si tun pè mi pẹlu ọba lati wá si ọdọ rẹ̀, 13 Ṣugbọn gbogbo wọnyi kò di nkankan fun mi, niwọ̀n igbati mo ba ri Mordekai, ara Juda nì, ti o joko li ẹnu ọ̀na ile ọba. 14 Nigbana ni Sereṣi aya rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ wi fun u pe, Jẹ ki a rì igi kan, ki o ga ni ãdọta igbọnwọ, ati li ọla ni ki o ba ọba sọ ọ ki a so Mordekai rọ̀ nibẹ: iwọ̀ o si fi ayọ̀ ba ọba lọ si ibi àse. Nkan yi dùn mọ Hamani, o si rì igi na.

Esteri 6

Ọba Dá Mordekai Lọ́lá

1 Li oru na ọba kò le sùn, o si paṣẹ pe, ki a mu iwe iranti, ani irohin awọn ọjọ wá, a si kà wọn niwaju ọba. 2 A si ri pe, ati kọ ọ pe, Mordekai ti sọ ti Bigtani, ati Tereṣi, awọn ìwẹfa ọba meji, oluṣọ iloro, awọn ẹniti nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba. 3 Ọba si wi pe, Iyìn ati ọlá wo li a fi fun Mordekai nitori eyi? Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba ti nṣe iranṣẹ fun u wi pe, a kò ṣe nkankan fun u. 4 Ọba si wi pe, Tani mbẹ ni àgbala? Hamani si ti de àgbala akọkàn ile ọba, lati ba ọba sọ ọ lati so Mordekai rọ̀ sori igi giga ti o ti rì fun u. 5 Awọn ọmọ-ọdọ ọba si wi fun u pe, Sa wò o, Hamani duro ni agbala, Ọba si wi pe, jẹ ki o wọle. 6 Bẹ̃ni Hamani si wọle wá, Ọba si wi fun u pe, kini a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun? Njẹ Hamani rò ninu ọkàn ara rẹ̀ pe, Tani inu ọba le dùn si lati bù ọlá fun jù emi tikalami lọ? 7 Hamani si da ọba lohùn pe, ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. 8 Jẹ ki a mu aṣọ ọba ti ọba ima wọ̀, ati ẹṣin ti ọba ima gùn, ati ade ọba ti ima gbe kà ori rẹ̀ wá; 9 Ki a si fi ẹ̀wu ati ẹṣin yi le ọwọ ọkan ninu awọn ijoye ọba ti o lọlajùlọ, ki nwọn fi ṣe ọṣọ fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun, ki o si mu u gẹṣin là igboro ilu, ki o si ma kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. 10 Nigbana ni ọba wi fun Hamani pe, yara kánkán, mu ẹ̀wu ati ẹṣin na, bi iwọ ti wi, ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun Mordekai, ara Juda nì, ti njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba: ohunkohun kò gbọdọ yẹ̀ ninu ohun ti iwọ ti sọ. 11 Nigbana ni Hamani mu aṣọ ati ẹṣin na, o si ṣe Mordekai li ọṣọ́, o si mu u là igboro ilu lori ẹṣin, o si kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. 12 Mordekai si tun pada wá si ẹnu-ọ̀na ile ọba, ṣugbọn Hamani yara lọ si ile rẹ̀ ti on ti ibinujẹ, o si bò ori rẹ̀. 13 Hamani si sọ gbogbo ohun ti o ba a, fun Sereṣi obinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn enia rẹ̀, amoye, ati Sereṣi obinrin rẹ̀, wi fun u pe, Bi Mordekai ba jẹ iru-ọmọ awọn Ju, niwaju ẹniti iwọ ti bẹ̀rẹ si iṣubu na, iwọ, kì yio le bori rẹ̀, ṣugbọn iwọ o ṣubu niwaju rẹ̀ dandan.

Wọ́n Pa Hamani

14 Bi nwọn si ti mba a sọ̀rọ lọwọ, awọn ìwẹfa ọba de, lati wá mu Hamani yára wá si ibi àse ti Esteri sè.

Esteri 7

1 Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá iba Esteri ayaba jẹ àse. 2 Ọba si tun wi fun Esteri ni ijọ keji ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini pe, kini ẹbẹ rẹ, Esteri ayaba? a o si fi fun ọ: ki si ni ibère rẹ? a o si ṣe e, ani lọ ide idaji ijọba. 3 Nigbana ni Esteri ayaba dahùn wi pe, bi mo ba ri ore-ọfẹ loju rẹ ọba, bi o ba si wù ọba, mo bẹbẹ ki a fi ẹmi mi bùn mi nipa ẹbẹ mi, ati awọn enia mi nipa ibère mi. 4 Nitori a ti tà wa, emi ati awọn enia mi, lati run wa, lati pa wa, ki a le parun. Ṣugbọn bi o ṣe pe, a ti tà wa fun ẹrúkunrin, ati ẹrúbirin ni, emi iba pa ẹnu mi mọ́, bi o tilẹ jẹ pe ọta na kò le di ofò ọba. 5 Nigbana ni Ahaswerusi ọba dahùn, o si wi fun Esteri ayaba pe, Tali oluwa rẹ̀ na, nibo li o si wà, ti o jẹ gbe e le ọkàn rẹ̀ lati ṣe bẹ̃? 6 Esteri si wi pe, ọlọtẹ enia ati ọta na ni Hamani, ẹni buburu yi. Nigbana ni ẹ̀ru ba Hamani niwaju ọba ati ayaba. 7 Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on. 8 Nigbana ni ọba pẹhinda lati inu àgbala ãfin sinu ibiti nwọn ti nmu ọti-waini, Hamani si ṣubu le ibi ìrọgbọkú lori eyi ti Esteri joko; nigbana ni ọba wi pe, yio ha tẹ́ ayaba lọdọ mi ninu ile bi? Bi ọ̀rọ na ti ti ẹnu ọba jade, nwọn bò oju Hamani. 9 Harbona ọkan ninu awọn ìwẹfa si wi niwaju ọba pe, Sa wò o, igi ti o ga ni ãdọta igbọnwọ ti Hamani ti rì nitori Mordekai ti o ti sọ ọ̀rọ rere fun ọba, o wà li oró ni ile Hamani. Ọba si wi pe, Ẹ so o rọ̀ lori rẹ̀. 10 Bẹ̃ni nwọn so Hamani rọ̀ sori igi ti o ti rì fun Mordekai; ibinu ọba si rọ̀.

Esteri 8

Wọ́n fún Àwọn Juu Láṣẹ láti Bá Àwọn Ọ̀tá Wọn Jà

1 Ni ijọ na ni Ahaswerusi ọba fi ile Hamani ọta awọn Ju, jìn Esteri, ayaba; Mordekai si wá siwaju ọba; nitori Esteri ti sọ bi o ti ri si on. 2 Ọba si bọ́ oruka rẹ̀, ti o ti gbà lọwọ Hamani, o si fi i fun Mordekai. Esteri si fi Mordekai ṣe olori ile Hamani. 3 Esteri si tun sọ niwaju ọba, o wolẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀, o si fi omijé bẹ̀ ẹ pe, ki o mu buburu Hamani, ara Agagi kuro, ati ete ti o ti pa si awọn Ju. 4 Nigbana ni ọba nà ọpá-alade wura si Esteri. Bẹ̃ni Esteri dide, o si duro niwaju ọba. 5 O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba. 6 Nitori pe, emi ti ṣe le ri ibi ti yio wá ba awọn enia mi? tabi emi ti ṣe le ri iparun awọn ibatan mi? 7 Nigbana ni Ahaswerusi ọba wi fun Esteri ayaba, ati fun Mordekai ara Juda na pe, Sa wò o, emi ti fi ile Hamani fun Esteri; on ni nwọn si ti so rọ̀ lori igi, nitoripe o ti gbe ọwọ le awọn Ju. 8 Ẹnyin kọwe ẹ̀wẹ li orukọ ọba, nitori awọn Ju bi ẹnyin ti fẹ́, ki ẹ si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀: nitori iwe ti a ba fi orukọ ọba kọ, ti a ba si fi òruka ọba ṣe edidi, ẹnikan kò le yi i pada. 9 Nigbana li a si pè awọn akọwe ọba li akokò na ni oṣù kẹta, eyini ni oṣù Sifani, li ọjọ kẹtalelogun rẹ̀; a si kọ ọ gẹgẹ bi Mordekai ti paṣẹ si awọn Ju, ati si awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati olori awọn ìgberiko metadilãdoje, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède wọn ati si awọn Ju gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi ède wọn. 10 Orukọ Ahaswerusi ọba li a fi kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀; o si fi iwe wọnni rán awọn ojiṣẹ lori ẹṣin, ti o gùn ẹṣin yiyara, ani ibãka, ọmọ awọn abo ẹṣin. 11 Ninu eyiti ọba fi aṣẹ fun gbogbo awọn Ju, ti o wà ni ilu gbogbo, lati kó ara wọn jọ, ati lati duro gbà ẹmi ara wọn là, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo agbara awọn enia, ati ìgberiko na, ti o ba fẹ kọlu wọn, pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn obinrin ki o ṣegbe; ki nwọn ki o si kó ìni wọn fun ara wọn, 12 Li ọjọ kanṣoṣo ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, li ọjọ kẹtala, oṣù kejila ti iṣe oṣù Adari. 13 Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn. 14 Bẹ̃ni awọn ojiṣẹ́ ti nwọn gun ẹṣin yiyara ati ibãka jade lọ, nitori aṣẹ ọba, nwọn yara, nwọn sare. A si pa aṣẹ yi ni Ṣuṣani ãfin. 15 Mordekai si jade kuro niwaju ọba, ninu aṣọ ọba, alaro ati funfun, ati ade wura nla, ati ẹ̀wu okùn ọ̀gbọ kikuná, ati elese aluko; ayọ̀ ati inu didùn si wà ni ilu Ṣuṣani. 16 Awọn Ju si ni imọlẹ, ati inu didùn, ati ayọ̀ ati ọlá. 17 Ati ni olukulùku ìgberiko, ati ni olukuluku ilu nibikibi ti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, awọn Ju ni ayọ̀ ati inu-didùn, àse, ati ọjọ rere. Ọ̀pọlọpọ awọn enia ilẹ na si di enia Juda; nitori ẹ̀ru awọn Ju ba wọn.

Esteri 9

Àwọn Juu Pa Àwọn Ọ̀tá Wọn Run

1 Njẹ li oṣù kejila, eyini ni oṣù Adari, li ọjọ kẹtala rẹ̀, ti ofin ọba ati aṣẹ rẹ̀ sunmọle lati mu u ṣẹ, li ọjọ ti awọn ọta awọn Ju ti rò pe, awọn o bori wọn, (bi o tilẹ ti jẹ pe, ati yi i pada pe, ki awọn Ju ki o bori awọn ti o korira wọn;) 2 Awọn Ju kó ara wọn jọ ninu ilu wọn ninu gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, lati gbe ọwọ le iru awọn ti o nwá ifarapa wọn: ẹnikẹni kò si le kò wọn loju; nitori ẹ̀ru wọn bà gbogbo enia. 3 Gbogbo awọn olori ìgberiko, ati awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati awọn ti nṣe iṣẹ ọba, ràn awọn Ju lọwọ, nitori ẹ̀ru Mordekai bà wọn. 4 Nitori Mordekai tobi ni ile ọba, okiki rẹ̀ si kàn ja gbogbo ìgberiko: nitori ọkunrin yi Mordekai ntobi siwaju ati siwaju. 5 Bayi ni awọn Ju a fi idà ṣá gbogbo awọn ọta wọn pa, ni pipa ati piparun, nwọn si ṣe awọn ọta ti o korira wọn bi nwọn ti fẹ. 6 Ati ni Ṣuṣani ãfin awọn Ju pa ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin run. 7 Ati Farṣandata, ati Dalfoni, ati Aspata, 8 Ati Porata, ati Adalia, ati Aridata, 9 Ati Farmaṣta, ati Arisai, ati Aridai, ati Faisata, 10 Awọn ọmọ Hamani, ọmọ Medata, mẹwẹwa, ọta awọn Ju ni nwọn pa; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn. 11 Li ọjọ na a mu iye awọn ti a pa ni Ṣuṣani ãfin wá siwaju ọba. 12 Ọba si wi fun Esteri ayaba pe, Awọn Ju pa, nwọn si ti pa ẹ̃dẹgbẹta enia run ni Ṣuṣani ãfin, ati awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa: kini nwọn ha ṣe ni gbogbo ìgberiko ọba iyokù? nisisiyi kini ẹbẹ rẹ? a o si fi fun ọ tabi kini iwọ o si tun bère si i? a o si ṣe e. 13 Nigbana ni Esteri wipe, Bi o ba wù ọba, jẹ ki a fi aṣẹ fun awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani ki nwọn ki o ṣe li ọ̀la pẹlu gẹgẹ bi aṣẹ ti oni, ki a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀ lori igi. 14 Ọba si paṣẹ pe, ki a ṣe bẹ̃; a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani; a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀. 15 Nitorina awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹrinla oṣù Adari pẹlu, nwọn si pa ọ̃durun ọkunrin ni Ṣuṣani; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn. 16 Ṣugbọn awọn Ju miran, ti o wà ni ìgberiko ọba, kó ara wọn jọ, nwọn dide duro lati gbà ẹmi ara wọn là, nwọn si simi kuro lọwọ awọn ọta wọn, nwọn si pa ẹgbã mẹtadilogoji enia o le ẹgbẹrin ninu awọn ọta wọn, ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kan nkan wọn. 17 Li ọjọ kẹtala oṣù Adari, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀ ni nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati ayọ̀. 18 Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn. 19 Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀. 20 Mordekai si kọwe nkan wọnyi, o si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, si awọn ti o sunmọ etile, ati awọn ti o jina. 21 Lati fi eyi lelẹ larin wọn, ki nwọn ki o le ma pa ọjọ kẹrinla oṣù Adari, ati ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ mọ́ li ọdọdun. 22 Bi ọjọ lọwọ eyiti awọn Ju simi kuro ninu awọn ọta wọn, ati oṣù ti a sọ ibanujẹ wọn di ayọ̀, ati ọjọ ọ̀fọ di ọjọ rere; ki nwọn ki o le sọ wọn di ọjọ àse, ati ayọ̀, ati ọjọ ti olukuluku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀, ati ẹbun fun awọn talaka. 23 Awọn Ju si gbà lati ṣe bi nwọn ti bẹ̀rẹ si iṣe, ati bi Mordekai si ti kọwe si wọn. 24 Pe, Hamani ọmọ Medata, ara Agagi nì, ọta gbogbo awọn Ju ti gbiro lati pa awọn Ju run, o si ti da Puri, eyinì ni ibo, lati pa wọn, ati lati run wọn; 25 Ṣugbọn nigbati Esteri tọ̀ ọba wá, o fi iwe paṣẹ pe, ki ete buburu ti a ti pa si awọn Ju ki o le pada si ori on tikalarẹ̀, ati ki a so ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sori igi. 26 Nitorina ni nwọn ṣe npè ọjọ wọnni ni Purimu bi orukọ Puri. Nitorina gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ inu iwe yi, ati nitori gbogbo eyi ti oju wọn ti ri nitori ọ̀ran yi, ati eyiti o ti ba wọn, 27 Awọn Ju lanà rẹ̀, nwọn si gbà a kanri wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ati fun gbogbo awọn ti o dà ara wọn pọ̀ mọ wọn, pe ki o máṣe yẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọjọ mejeji wọnyi mọ́ gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi akokò wọn ti a yàn lọdọdun. 28 Ati pe, ki nwọn ma ranti ọjọ wọnyi, ki nwọn si ma kiyesi i ni irandiran wọn gbogbo; olukuluku idile, olukuluku ìgberiko, ati olukuluku ilu; ati pe, ki Purimu wọnyi ki o máṣe yẹ̀ larin awọn Ju, tabi ki iranti wọn ki o máṣe parun ninu iru-ọmọ wọn. 29 Nigbana ni Esteri ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Mordekai, ara Juda, fi ọlá gbogbo kọwe, lati fi idi iwe keji ti Purimu yi mulẹ. 30 O si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju, si ẹtadilãdoje ìgberiko ijọba Ahaswerusi, ọ̀rọ alafia ati otitọ. 31 Lati fi idi ọjọ Purimu wọnyi mulẹ, li akokò wọn ti a yàn gẹgẹ bi Mordekai, ara Juda, ati Esteri ayaba ti paṣẹ fun wọn, ati bi nwọn ti pinnu rẹ̀ fun ara wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ọ̀ran ãwẹ ati ẹkún wọn. 32 Aṣẹ Esteri si fi idi ọ̀ran Purimu yi mulẹ; a si kọ ọ sinu iwe.

Esteri 10

Títóbi Ahasu-erusi ati Modekai

1 AHASWERUSI ọba si fi owo ọba le ilẹ fun gbogbo ilẹ, ati gbogbo erekùṣu okun. 2 Ati gbogbo iṣe agbara rẹ̀, ati ti ipa rẹ̀, ati ìrohin titobi Mordekai, bi ọba ti sọ ọ di nla, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Media ati Persia? 3 Nitori Mordekai ara Juda li o ṣe igbakeji Ahaswerusi ọba, o si tobi ninu awọn Ju, o si ṣe itẹwọgbà lọdọ ọ̀pọlọpọ ninu awọn arakunrin rẹ̀, o nwá ire awọn enia rẹ̀, o si nsọ̀rọ alafia fun gbogbo awọn iru-ọmọ rẹ̀.

Jobu 1

Satani Dán Jobu Wò

1 ỌKUNRIN kan wà ni ilẹ Usi, orukọ ẹniti ijẹ Jobu; ọkunrin na si ṣe olõtọ, o duro ṣinṣin, ẹniti o si bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. 2 A si bi ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta fun u. 3 Ohunọ̀sin rẹ̀ si jẹ ẹdẹgbarin agutan, ati ẹgbẹdogun ibakasiẹ, ati ẹdẹgbẹta ajaga ọdámalu, ati ẹdẹgbẹta abokẹtẹkẹtẹ, o si pọ̀; bẹ̃li ọkunrin yi si pọ̀ jù gbogbo awọn ọmọ ara ila-õrun lọ. 4 Awọn ọmọ rẹ̀ a si ma lọ ijẹun àse ninu ile ara wọn, olukuluku li ọjọ rẹ̀; nwọn a si ma ranṣẹ pe arabinrin wọn mẹtẹta lati jẹun ati lati mu pẹlu wọn. 5 O si ṣe, nigbati ọjọ àse wọn pé yika, ni Jobu ranṣẹ lọ iyà wọn si mimọ, o si dide ni kùtukutu owurọ, o si rú ẹbọ sisun niwọn iye gbogbo wọn; nitoriti Jobu wipe: bọya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, nwọn kò si ṣọpẹ́ fun Ọlọrun lọkàn wọn. Bẹ̃ni Jobu imaṣe nigbagbogbo. 6 Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn. 7 Oluwa si bi Satani wipe: nibo ni iwọ ti wá? nigbana ni Satani da Oluwa lohùn wipe: ni ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye, ati ni irinkerindo ninu rẹ̀. 8 Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu. 9 Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi? 10 Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ. 11 Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ. 12 Oluwa si dá Satani lohùn wipe: kiyesi i, ohun gbogbo ti o ni mbẹ ni ikawọ rẹ, kìki on tikara rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ rẹ kàn: bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa.

Ọrọ̀ ati Àwọn Ọmọ Jobu Parun

13 O si di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati obinrin njẹ, ti nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin: 14 Onṣẹ kan si tọ̀ Jobu wá wipe: awọn ọda-malu ntulẹ, awọn kẹtẹkẹtẹ si njẹ li ẹba wọn; 15 Awọn ara Saba si kọlu wọn, nwọn si nkó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn ti fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa, emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati ròhin fun ọ. 16 Bi o ti nsọ li ẹnu; ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: iná nla Ọlọrun ti ọrun bọ́ si ilẹ, o si jó awọn agutan ati awọn iranṣẹ ni ajorun; emi nikanṣoṣo li o salà lati rohin fun ọ. 17 Bi o si ti nsọ li ẹnu, ẹnikan si de pẹlu ti o wipe: awọn ara Kaldea pingun si ọ̀na mẹta, nwọn si kọlu awọn ibakasiẹ, nwọn si kó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn si fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa; emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati rohin fun ọ. 18 Bi o ti nsọ li ẹnu, ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ọmọ rẹ obinrin njẹ nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin. 19 Si kiyesi i, ẹfufu nlanla ti iha ijù fẹ wá ikọlu igun mẹrẹrin ile, o si wolù awọn ọdọmọkunrin na, nwọn si kú, emi nikanṣoṣo li o yọ lati rohin fun ọ. 20 Nigbana ni Jobu dide, o si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, o si fari rẹ̀, o wolẹ, o si gbadura. 21 Wipe, Nihoho ni mo ti inu iya mi jade wá, nihoho ni emi o si tun pada lọ sibẹ: Oluwa fifunni Oluwa si gbà lọ, ibukun li orukọ Oluwa. 22 Ninu gbogbo eyi Jobu kò ṣẹ̀, bẹ̃ni kò si fi were pè Ọlọrun lẹjọ.

Jobu 2

Satani Tún Dán Jobu Wò

1 O si tun di ijọ kan nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn, lati pé niwaju Oluwa. 2 Oluwa si bi Satani pe, nibo ni iwọ ti wá? Satani si dá Oluwa lohùn pe, lati ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye ati ni irinkerindo ninu rẹ̀. 3 Oluwa si wi fun Satani pe, iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ti o si korira ìwa buburu, bẹ̃li o si di ìwa otitọ rẹ̀ mu ṣinṣin, bi iwọ tilẹ ti dẹ mi si i lati run u lainidi. 4 Satani si dá Oluwa lohùn wipe, awọ fun awọ; ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀. 5 Ṣugbọn nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ egungun rẹ̀ ati ara rẹ̀, bi kì yio si bọhùn li oju rẹ. 6 Oluwa si wi fun Satani pe, Wõ, o mbẹ ni ikawọ rẹ, ṣugbọn dá ẹmi rẹ̀ si. 7 Bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa, o si sọ Jobu li õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de atari rẹ̀. 8 O si mu apadì o fi nhá ara rẹ̀, o si joko ninu ẽru. 9 Nigbana ni aya rẹ̀ wi fun u pe, iwọ di ìwa otitọ rẹ mu sibẹ! bu Ọlọrun, ki o si kú. 10 Ṣugbọn on da a lohùn pe, iwọ sọ̀rọ bi ọkan ninu awọn obinrin alaimoye ti isọ̀rọ; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi! Ninu gbogbo eyi Jobu kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.

Àwọn Ọ̀rẹ́ Jobu Wá

11 Nigbati awọn ọrẹ Jobu mẹta gburo gbogbo ibi ti o ba a, nwọn wá, olukuluku lati ibujoko rẹ̀ wá; Elifasi, ara Tema, a si Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama: nitoripe nwọn ti dajọ ipade pọ̀ lati ba a ṣọ̀fọ on ati ṣipẹ fun u. 12 Nigbati nwọn si gboju wọn wò li òkere rére, ti nwọn kò si mọ̀ ọ, nwọn gbe ohùn wọn soke, nwọn sọkun: olukuluku si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, nwọn si kù erupẹ si oju ọrun si ara wọn lori. 13 Bẹ̃ni nwọn joko tì i ni ilẹyilẹ ni ijọ meje ti ọ̀san ti oru, ẹnikẹni kò si ba a dá ọ̀rọ kan sọ nitoriti nwọn ri pe, ibinujẹ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.

Jobu 3

Jobu Ráhùn sí Ọlọrun

1 LẸHIN eyi ni Jobu yanu o si fi ọjọ ibi rẹ̀ ré. 2 Jobu sọ, o si wipe, 3 Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan. 4 Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i. 5 Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya. 6 Ki òkunkun ki o ṣúbo oru na biribiri, ki o má ṣe yọ̀ pẹlu ọjọ ọdun na: ki a má ṣe kà a mọ iye ọjọ oṣù. 7 Ki oru na ki o yàgan; ki ohùn ayọ̀ kan ki o má ṣe wọnu rẹ̀ lọ. 8 Ki awọn ti ifi ọjọ gegun ki o fi i gegun, ti nwọn muratan lati rú Lefiatani soke. 9 Ki irawọ̀ ofẽfe ọjọ rẹ̀ ki o ṣokùnkun; ki o ma wá imọlẹ, ṣugbọn ki o má si, bẹ̃ni ki o má ṣe ri afẹmọjumọ́. 10 Nitoriti kò se ilẹkun inu iya mi, bẹ̃ni kó si pa ibinujẹ mọ́ kuro li oju mi. 11 Ẽṣe ti emi kò fi kú lati inu wá, tabi ti emi kò fi pin ẹmi nigbati mo ti inu jade wá? 12 Ẽṣe ti ẽkun wá pade mi, tabi ọmu ti emi o mu? 13 Njẹ! nisisiyi, emi iba ti dubulẹ̀ jẹ, emi a si dakẹ, emi iba ti sùn: njẹ emi iba ti simi! 14 Pẹlu awọn ọba ati igbimọ aiye, ti o mọle takete fun ara wọn. 15 Tabi pẹlu awọn ọmọ-alade ti o ni wura, ti nwọn si fi fadakà kún inu ile wọn. 16 Tabi bi ọlẹ̀ ti a sin, emi kì ba ti si; bi ọmọ iṣẹnu ti kò ri imọlẹ. 17 Nibẹ ni ẹni-buburu ṣiwọ iyọnilẹnu, nibẹ ẹni-ãrẹ̀ wà ninu isimi. 18 Nibẹ ni awọn ìgbekun simi pọ̀, nwọn kò si gbohùn amunisìn mọ́. 19 Ati ewe ati àgba wà nibẹ, ẹru si di omnira kuro lọwọ olowo rẹ̀. 20 Nitori kili a ṣe fi imọlẹ fun otoṣi, ati ìye fun ọlọkàn kikoro. 21 Ti nwọn duro de ikú, ṣugbọn on kò wá, ti nwọn wàlẹ wá a jù fun iṣura ti a bò mọlẹ pamọ. 22 Ẹniti o yọ̀ gidigidi, ti inu wọn si dùn nigbati nwọn ba le wá isa-okú ri. 23 Kili a fi imọlẹ fun ẹniti ọ̀na rẹ̀ lumọ si, ti Ọlọrun si sọgba di mọ ká? 24 Nitoripe imi-ẹ̀dun mi ṣaju ki nto jẹun, ikerora mi si tú jade bi omi. 25 Nitoripe ohún na ti mo bẹ̀ru gidigidi li o de ba mi yi, ẹ̀ru ohun ti mo bà li o si de si mi yi. 26 Emi kò wà lailewu rí, bẹ̃li emi kò ni isimi, bẹ̃li emi kò ni ìfaiyabalẹ, asiwá-asibọ̀ iyọnu de.

Jobu 4

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni

1 NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, 2 Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ? 3 Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le. 4 Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera. 5 Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀. 6 Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ? 7 Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri? 8 Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na. 9 Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun. 10 Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka. 11 Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri. 12 Njẹ nisisiyi a fi ohun lilumọ́ kan hàn fun mi, eti mi si gbà diẹ ninu rẹ̀. 13 Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia. 14 Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé. 15 Nigbana ni iwin kan kọja lọ niwaju mi, irun ara mi dide ró ṣanṣan. 16 On duro jẹ, ṣugbọn emi kò le iwò apẹrẹ irí rẹ̀, àworan kan hàn niwaju mi, idakẹ rọrọ wà, mo si gbohùn kan wipe: 17 Ẹni kikú le jẹ olododo niwaju Ọlọrun, enia ha le mọ́ ju Ẹlẹda rẹ̀ bi? 18 Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ. 19 Ambọtori awọn ti ngbe inu ile amọ̀, ẹniti ipilẹ wọn jasi erupẹ ti yio di rirun kòkoro. 20 A npa wọn run lati òwurọ di alẹ́, nwọn gbe lailai lairi ẹni kà a si. 21 A kò ha ke okùn iye wọn kuro bi? nwọn ku, ani lailọgbọn.

Jobu 5

1 NJẸ pè nisisiyi! bi ẹnikan ba wà ti yio da ọ lohùn, tabi tani ninu awọn ẹni-mimọ́ ti iwọ o wò? 2 Nitoripe ibinu pa alaimoye, irúnu a si pa òpe enia. 3 Emi ti ri alaimoye ti o ta gbongbò mulẹ̀, ṣugbọn lojukanna mo fi ibujoko rẹ̀ bú. 4 Awọn ọmọ rẹ̀ kò jina sinu ewu, a si tẹ̀ wọn mọlẹ loju ibode, bẹ̃ni kò si alãbò kan. 5 Ikore oko ẹniti awọn ẹniti ebi npa jẹrun, ti nwọn si wọnú ẹ̀gun lọ ikó, awọn igara si gbe ohùn ini wọn mì. 6 Bi ipọnju kò tilẹ̀ tinu erupẹ jade wá nì, ti iyọnu kò si tinu ilẹ hù jade wá. 7 Ṣugbọn a bi enia sinu wàhala, gẹgẹ bi ìpẹpẹ iná ti ima ta sokè. 8 Sọdọ Ọlọrun li emi lè ma ṣe awári, li ọwọ Ọlọrun li emi lè ma fi ọ̀ran mi le. 9 Ẹniti o ṣe ohun ti o tobi, ti a kò lè iṣe awári, ohun iyanu laini iye. 10 Ti nrọ̀jo si ilẹ aiye, ti o si nrán omi sinu ilẹ̀kilẹ. 11 Lati gbe awọn onirẹlẹ leke, ki a le igbé awọn ẹni ibinujẹ ga si ibi ailewu. 12 O yi ìmọ awọn alarekerekè po, bẹ̃li ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ. 13 O mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke ara wọn, ati ìmọ awọn onroro li o tãri ṣubu li ògedengbè. 14 Nwọn sure wọ inu òkunkun li ọ̀san, nwọn si nfọwọ talẹ̀ li ọ̀sangangan bi ẹnipe li oru. 15 Ṣugbọn o gba talakà là kuro li ọwọ idà, lọwọ ẹnu wọn, ati lọwọ awọn alagbara. 16 Bẹ̃ni abá wà fun talaka, aiṣotitọ si pa ẹnu rẹ̀ mọ. 17 Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare. 18 Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina. 19 Yio gbà ọ ninu ipọnju mẹfa, ani ninu meje ibi kan kì yio ba ọ. 20 Ninu ìyan yio gbà ọ lọwọ ikú, ati ninu ogun yio gbà ọ lọwọ idà. 21 A o pa ọ mọ kuro lọwọ ìna ahọn, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru iparun nigbati o ba dé. 22 Ẹrin iparun ati ti iyàn ni iwọ o rín, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru ẹranko ilẹ aiye. 23 Nitoripe iwọ o ba okuta ìgbẹ mulẹ̀, awọn ẹranko ìgbẹ yio wà pẹlu rẹ li alafia. 24 Iwọ o si mọ̀ pe alafia ni ibujoko rẹ wà, iwọ o si ma ṣe ibẹ̀wo ibujoko rẹ, iwọ kì yio ṣìna. 25 Iwọ o si mọ̀ pẹlu pe iru-ọmọ rẹ yio si pọ̀, ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ yio ri bi koriko ìgbẹ. 26 Iwọ o wọ isa-okú rẹ lọ li ògbologbo ọjọ bi apo-ọka ti o gbó, ti a si nko ni igbà ikore rẹ̀. 27 Kiyesi i, awa ti nwadi rẹ̀, bẹ̃li o ri! gbà a gbọ́, ki o si mọ̀ pe fun ire ara rẹ ni!

Jobu 6

1 JOBU si dahùn o si wipe, 2 A! a ba le iwọ̀n ibinujẹ mi ninu òṣuwọn, ki a si le igbe ọ̀fọ mi le ori òṣuwọn ṣọkan pọ̀! 3 Njẹ nisisiyi, iba wuwo jù iyanrin okun lọ: nitorina li ọ̀rọ mi ṣe ntàse. 4 Nitoripe ọfa Olodumare wọ̀ mi ninu, oró eyiti ọkàn mi mu; ipaiya-ẹ̀ru Ọlorun dotì mi. 5 Kẹtẹkẹtẹ ìgbẹ a ma dún, nigbati o ba ni koriko, tabi ọdá-malu a ma dún sori ijẹ rẹ̀? 6 A le jẹ ohun ti kò li adùn li aini iyọ̀, tabi adùn wà ninu funfun ẹyin? 7 Ohun ti ọkàn mi kọ̀ lati tọ́, on li o dàbi onjẹ mi ti kò ni adùn. 8 A! emi iba lè ri iberè mi gbà; ati pe, ki Ọlọrun le fi ohun ti emi ṣafẹri fun mi. 9 Ani, Ọlọrun iba jẹ pa mi run, ti on iba jẹ ṣiwọ rẹ̀ ki o si ké mi kuro. 10 Nigbana ni emi iba ni itunú sibẹ, ani emi iba mu ọkàn mi le ninu ibinujẹ mi ti kò da ni si: nitori emi kò fi ọ̀rọ Ẹni Mimọ́ nì sin ri. 11 Kili agbara mi ti emi o fi dabá? ki si li opin mi ti emi o fi fà ẹmi mi gùn? 12 Agbara mi iṣe agbara okuta bi, tabi ẹran ara mi iṣe idẹ? 13 Iranlọwọ mi kò ha wà ninu mi: ọgbọn ha ti salọ kuro lọdọ mi bi? 14 Ẹniti aya rẹ̀ yọ́ danu tan ni a ba ma ṣãnu fun lati ọdọ ọrẹ rẹ̀ wá, ki o má kọ̀ ibẹru Olodumare silẹ̀. 15 Awọn ará mi ṣẹ̀tan bi odò ṣolõ, bi iṣàn gburu omi odò ṣolõ, nwọn ṣàn kọja lọ. 16 Ti o dúdu nitori omi didì, ati nibiti òjo didì gbe lùmọ si. 17 Nigbakũgba ti nwọn ba gboná, nwọn a si yọ́ ṣanlọ, nigbati õrùn ba mú, nwọn si gbẹ kurò ni ipò wọn. 18 Iya ọ̀na wọn a si yipada sapakan, nwọn goke si ibi asan, nwọn si run. 19 Ẹgbẹ ogun Tema nwoye, awọn ọwọ́-èro Seba duro de wọn. 20 Nwọn dãmu, nitoriti nwọn ni abá; nwọn debẹ̀, nwọn si dãmu. 21 Njẹ nisisiyi, ẹnyin dabi wọn; ẹnyin ri irẹ̀silẹ mi, aiya si fò nyin. 22 Emi ha wipe, ẹ mu ohun fun mi wá, tabi pe, ẹ bun mi ni ẹ̀bun ninu ohun ini nyin? 23 Tabi, ẹ gbà mi li ọwọ ọ̀ta nì, tabi, ẹ rà mi padà kuro lọwọ alagbara nì! 24 Ẹ kọ́ mi, emi o si pa ẹnu mi mọ́; ki ẹ si mu mi moye ibiti mo gbe ti ṣìna. 25 Wo! bi ọ̀rọ otitọ ti li agbara to! ṣugbọn kini aròye ibawi nyin jasi? 26 Ẹnyin ṣebi ẹ o ba ọ̀rọ ati ohùn ẹnu ẹniti o taku wi, ti o dabi afẹfẹ. 27 Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin. 28 Nitorina ki eyi ki o tó fun nyin: ẹ ma wò mi! nitoripe o hàn gbangba pe: li oju nyin ni emi kì yio ṣeke. 29 Emi bẹ̀ nyin, ẹ pada, ki o má ṣe jasi ẹ̀ṣẹ: ani ẹ si tun pada, are mi mbẹ ninu ọ̀ran yi. 30 Aiṣedede ha wà li ahọn mi? njẹ itọwò ẹnu mi kò kuku le imọ̀ ohun ti o burujù?

Jobu 7

1 NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe? 2 Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀. 3 Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi. 4 Nigbati mo dubulẹ̀, emi wipe, nigbawo ni emi o dide, ti oru yio si kọja? o si tó fun mi lati yi sihin yi sọhun titi yio fi di afẹmọ́jumọ. 5 Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni. 6 Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti. 7 A! ranti pe afẹfẹ li ẹmi mi; oju mi kì yio pada ri rere mọ. 8 Oju ẹniti o ri mi, kì yio ri mi mọ; oju rẹ tẹ mọra mi, emi kò sí mọ́! 9 Bi awọ-sanma ti iparun, ti isi fò lọ, bẹ̃li ẹniti nlọ si ipò-okú, ti kì yio pada wá mọ. 10 Kì yio pada sinu ile rẹ̀ mọ, bẹ̃ni ipò rẹ̀ kì yio mọ̀ ọ mọ. 11 Nitorina emi kì yio pa ẹnu mi mọ, emi o ma sọ ninu irora ọkàn mi, emi o ma ṣe irahùn ninu kikoro ọkàn mi. 12 Emi ama iṣe ejo okun tabi erinmi, ti iwọ fi yàn oluṣọ tì mi? 13 Nigbati mo wipe, ibusùn mi yio tù mi lara, itẹ mi yio gbé ẹrù irahùn mi pẹlu. 14 Nigbana ni iwọ fi alá da mi niji, iwọ si fi iran oru dẹrubà mi. 15 Bẹ̃li ọkàn mi yan isà okú jù aye, ikú jù egungun mi lọ. 16 O su mi, emi kò le wà titi: jọwọ mi jẹ, nitoripe asan li ọjọ mi. 17 Kili enia ti iwọ o ma kokìki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e? 18 Ati ti iwọ o fi ma wa ibẹ̀ ẹ wò li orowurọ̀, ti iwọ o si ma dán a wò nigbakũgba! 19 Yio ti pẹ́ to ki iwọ ki o to fi mi silẹ̀ lọ, ti iwọ o fi jọ mi jẹ titi emi o fi le dá itọ mi mì. 20 Emi ti ṣẹ̀, kili emi o ṣe si ọ, iwọ Olùtọju enia? ẽṣe ti iwọ fi fi mi ṣe àmi itasi niwaju rẹ, bẹ̃li emi si di ẹrù-wuwo si ara rẹ? 21 Ẽṣe ti iwọ kò si dari irekọja mi jì, ki iwọ ki o si mu aiṣedede mi kuro? njẹ nisisiyi li emi iba sùn ninu erupẹ, iwọ iba si wá mi kiri li owurọ̀, emi ki ba ti si.

Jobu 8

1 NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe, 2 Iwọ o ti ma sọ nkan wọnyi pẹ to? ti ọ̀rọ ẹnu rẹ yio si ma dabi ẹfufu nla? 3 Ọlọrun a ha ma yi idajọ po bi, tabi Olodumare a ma fi otitọ ṣẹ̀ bi? 4 Nigbati awọn ọmọ rẹ ṣẹ̀ si i, o si gbá wọn kuro nitori irekọja wọn. 5 Bi iwọ ba si kepe Ọlọrun ni igba akokò, ti iwọ bá si gbadura ẹ̀bẹ si Olodumare. 6 Iwọ iba mọ́, ki o si duro ṣinṣin: njẹ nitõtọ nisisiyi on o tají fun ọ, on a si sọ ibujoko ododo rẹ di pipọ. 7 Ipilẹṣẹ rẹ iba tilẹ kere ri, bẹ̃ni igbẹhin rẹ iba pọ̀ si i gidigidi. 8 Emi bẹ̀ ọ njẹ, bere lọwọ awọn ara igbãni, ki o si kiyesi iwádi awọn baba wọn. 9 Nitoripe ọmọ-àná li awa, a kò si mọ̀ nkan, nitoripe òjiji li ọjọ wa li aiye. 10 Awọn kì yio ha kọ́ ọ, nwọn kì yio si sọ fun ọ, nwọn kì yio si sọ̀rọ lati inu ọkàn wọn jade wá? 11 Koriko odò ha le dàgba laini ẹrẹ̀, tabi ẽsú ha le dàgba lailomi? 12 Nigbati o wà ni tutù, ti a kò ke e lulẹ̀, o rọ danu sin eweko miran gbogbo. 13 Bẹ̃ni ipa ọ̀na gbogbo awọn ti o gbagbe Ọlọrun, abá awọn àgabàgebe yio di ofo. 14 Abá ẹniti a o ke kuro, ati igbẹkẹle ẹniti o dàbi ile alantakùn. 15 Yio fi ara tì ile rẹ̀, ṣugbọn kì yio le iduro, yio fi di ara rẹ̀ mu ṣinṣin ṣugbọn kì yio le iduro pẹ. 16 O tutù niwaju õrùn, ẹka rẹ̀ si yọ jade ninu ọgbà rẹ̀. 17 Gbòngbo rẹ̀ ta yi ebè ka, o si wò ibi okuta wọnni. 18 Bi o ba si pa a run kuro ni ipò rẹ̀, nigbana ni ipò na yio sẹ ẹ pe: emi kò ri ọ ri! 19 Kiyesi eyi ni ayọ̀ ọ̀na rẹ̀ ati lati inu ilẹ li omiran yio ti hù jade wá. 20 Kiyesi i, Ọlọrun kì yio ta ẹni-otitọ nù, bẹ̃ni kì yio ràn oniwa-buburu lọwọ. 21 Titi yio fi fi ẹ̀rin kún ọ li ẹnu, ati ète rẹ pẹlu iho ayọ̀. 22 Itiju li a o fi bò awọn ti o korira rẹ, ati ibujoko enia buburu kì yio si mọ.

Jobu 9

1 JOBU si dahùn o si wipe, 2 Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun? 3 Bi o ba ṣepe yio ba a jà, on kì yio lè idá a lohùn kan ninu ẹgbẹrun ọ̀ran. 4 Ọlọgbọ́n-ninu ati alagbara ni ipá li on; tali o ṣagidi si i, ti o si gbè fun u ri? 5 Ẹniti o ṣi okè ni idi, ti nwọn kò si mọ̀: ti o tari wọn ṣubu ni ibinu rẹ̀. 6 Ti o mì ilẹ aiye tìti kuro ni ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ si mì tìti. 7 Ti o paṣẹ fun õrùn, ti on kò si là, ti o si dí irawọ̀ mọ́. 8 On nikanṣoṣo li o na oju ọrun lọ, ti o si nrìn lori ìgbì okun. 9 Ẹniti o da irawọ̀ Arketuru, Orioni ati Pleiade ati iyàra pipọ ti gusu. 10 Ẹniti nṣe ohun ti o tobi jù awari lọ, ani ohun iyanu laini iye. 11 Kiyesi i, on kọja lọ li ẹ̀ba ọdọ mi, emi kò si ri i, o si kọja siwaju, bẹ̃li emi kò ri oju rẹ̀. 12 Kiyesi i, o jãgbà lọ, tani yio fa a pada? tani yio bi i pe, kini iwọ nṣe nì? 13 Ọlọrun kò ni fà ibinu rẹ̀ sẹhin, awọn oniranlọwọ ìgberaga a si tẹriba labẹ rẹ̀. 14 Ambọtori emi ti emi o fi dá a lohùn, ti emi o fi má ṣa ọ̀rọ awawì mi ba a ṣawiye? 15 Bi o tilẹ ṣepe mo ṣe olododo, emi kò gbọdọ̀ da a lohùn, ṣugbọn emi o gbadura ẹ̀bẹ mi sọdọ onidajọ mi. 16 Bi emi ba si kepè e, ti on si da mi lohùn, emi kì yio si gbagbọ pe, on ti feti si ohùn mi. 17 Nitoripe o fi ẹ̀fufu nla ṣẹ mi tutu, o sọ ọgbẹ mi di pipọ lainidi. 18 On kì yio jẹ ki emi ki o fà ẹmi mi, ṣugbọn o fi ohun kikorò kún u fun mi. 19 Bi mo ba sọ ti agbara, wò o! alagbara ni, tabi niti idajọ, tani yio da akoko fun mi lati rò? 20 Bi mo tilẹ da ara mi lare, ẹnu ara mi ni yio dá mi lẹbi; bi mo wipe, olododo li emi, yio si fi mi hàn ni ẹni-òdi. 21 Olõtọ ni mo ṣe, sibẹ emi kò kiyesi ẹmi mi, ìwa mi li emi iba ma gàn. 22 Ohun kanna ni, nitorina ni emi ṣe sọ ọ: on a pa ẹni-otitọ ati enia buburu pẹlu. 23 Bi jamba ba pa ni lojijì, yio rẹrin idanwo alaiṣẹ̀. 24 A fi aiye le ọwọ enia buburu; o si bò awọn onidajọ rẹ̀ li oju; bi kò ba ri bẹ̃, njẹ tani? 25 Njẹ nisisiyi ọjọ mi yara jù onṣẹ lọ, nwọn fò lọ, nwọn kò ri ire. 26 Nwọn kọja lọ bi ọkọ-ẽsú ti nsure lọ; bi idì ti o nyara si ohun ọdẹ. 27 Bi emi ba wipe, emi o gbagbe aro ibinujẹ mi, emi o fi ọkàn lelẹ̀, emi o si rẹ̀ ara mi lẹkun. 28 Ẹ̀ru ibinujẹ mi gbogbo bà mi, emi mọ̀ pe iwọ kì yio mu mi bi alaiṣẹ̀. 29 Bi o ba ṣepe enia buburu li emi, njẹ kili emi nṣe lãlã lasan si! 30 Bi mo tilẹ fi omi òjo didì wẹ̀ ara mi, ti mo fi omi-aró wẹ̀ ọwọ mi mọ́, 31 Sibẹ iwọ o gbe mi bọ̀ inu ihò ọ̀gọdọ, aṣọ ara mi yio sọ mi di ẹni-irira. 32 Nitori on kì iṣe enia bi emi, ti emi o fi da a lohùn ti awa o fi pade ni idajọ. 33 Bẹ̃ni kò si alatunṣe kan lagbedemeji wa, ti iba fi ọwọ rẹ̀ le awa mejeji lara. 34 Ki on sa mu ọ̀pa rẹ̀ kuro lara mi, ki ìbẹru rẹ̀ ki o má si ṣe daiya fò mi. 35 Nigbana ni emi iba sọ̀rọ, emi kì ba si bẹ̀ru rẹ̀; ṣugbọn kò ri bẹ̃ fun mi.

Jobu 10

1 AGARA ìwa aiye mi da mi tan, emi o tú aroye mi sode lọdọ mi, emi o ma sọ ninu kikorò ibinujẹ ọkàn mi. 2 Emi o wi fun Ọlọrun pe, o jare! máṣe dá mi lẹbi; fi hàn mi nitori idi ohun ti iwọ fi mba mi jà. 3 O ha tọ́ si ọ ti iwọ iba ma tẹ̀mọlẹ̀, ti iwọ iba fi ma gan iṣẹ ọwọ rẹ, ti iwọ o fi ma tan imọlẹ si ìmọ enia buburu? 4 Oju rẹ iha ṣe oju enia bi? tabi iwọ a ma riran bi enia ti iriran? 5 Ọjọ rẹ ha dabi ọjọ enia, ọdun rẹ ha dabi ọdun enia? 6 Ti iwọ fi mbere aiṣedẽde mi, ti iwọ si fi wa ẹ̀ṣẹ mi ri? 7 Iwọ mọ̀ pe emi kì iṣe oniwa-buburu, kò si sí ẹniti igbà kuro li ọwọ rẹ. 8 Ọwọ rẹ li o ti dá mi, ti o si mọ mi pọ̀ yikakiri; sibẹ iwọ si mbà mi jẹ́. 9 Emi bẹ̀ ọ ranti pe iwọ ti mọ mi bi amọ̀; iwọ o ha si tun mu mi pada lọ sinu erupẹ? 10 Iwọ kò ha ti tu mi dà jade bi wàra, iwọ kò si mu mi dipọ̀ bi wàrakasi? 11 Iwọ sa ti fi awọ ati ẹran-ara wọ̀ mi, iwọ si fi egungun ati iṣan ṣọgbà yi mi ká. 12 Iwọ ti fun mi li ẹmi ati oju rere, ibẹ̀wo rẹ si pa ọkàn mi mọ́. 13 Nkan wọnyi ni iwọ si ti fi pamọ ninu rẹ; emi mọ̀ pe, eyi mbẹ lọdọ rẹ. 14 Bi mo ba ṣẹ̀, nigbana ni iwọ sàmi si mi, iwọ kì yio si dari aiṣedede mi ji. 15 Bi mo ba ṣe ẹni-buburu, egbé ni fun mi! bi mo ba si ṣe ẹni-rere, bẹ̃li emi kò si le igbe ori mi soke. Emi damu, mo si wo ipọnju mi. 16 Nitoriti npọ̀ si i: iwọ ndẹ mi kiri bi kiniun; ati pẹlu, iwọ a si fi ara rẹ hàn fun mi ni iyanju. 17 Iwọ si tun sọ awọn ẹlẹri rẹ si mi di ọtun, iwọ si sọ irunu rẹ di pipọ si mi, ayipada ati ogun dó tì mi. 18 Njẹ nitorina iwọ ha ṣe bí mi jade lati inu wá? A! emi iba kúku ti kú, ojukoju kì ba ti ri mi! 19 Emi iba dabi ẹniti kò si ri, a ba ti gbe mi lati inu lọ si isà-okú. 20 Ọjọ mi kò ha kuru bi? dawọ duro, ki o si jọwọ mi jẹ ki emi fi aiya balẹ diẹ. 21 Ki emi ki o to lọ sibi ti emi kì yio pada sẹhin mọ́, ani si ilẹ òkunkun ati ojiji ikú. 22 Ilẹ òkunkun bi òkunkun tikararẹ̀, ati ti ojiji ikú, laini èto, nibiti imọlẹ dabi òkunkun.

Jobu 11

1 NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe, 2 A le iṣe ki a má ṣe dahùn si ọ̀pọlọpọ ọ́rọ, a ha si le dare fun ẹniti ẹnu rẹ̃ kún fun ọ̀rọ sisọ? 3 Amọ̀tan rẹ le imu enia pa ẹnu wọn mọ bi? bi iwọ ba yọṣuti si ni, ki ẹnikẹni ki o má si doju tì ọ bi? 4 Nitori iwọ sa ti wipe, ọ̀rọ ẹkọ́ mi mọ́, emi si mọ́ li oju rẹ. 5 Ṣugbọn o ṣe! Ọlọrun iba jẹ sọ̀rọ, ki o si ya ẹnu rẹ̀ si ọ lara. 6 Ki o si fi aṣiri ọgbọ́n hàn ọ pe, o pọ̀ jù oye enia lọ; nitorina mọ̀ pe: Ọlọrun kò bere to bi ẹbi rẹ. 7 Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? iwọ le ri idi Olodumare de pipé rẹ̀? 8 O dabi giga ọrun, kini iwọ le iṣe? o jinlẹ jù ipo-okú lọ, kini iwọ le imọ̀? 9 Ìwọn rẹ̀ gùn jù aiye lọ, o si ni ìbu jù okun lọ. 10 Bi on ba rekọja, ti o si sénà, tabi ti o si ṣe ikojọpọ, njẹ tani yio da a pada kuro? 11 On sa mọ̀ enia asan, o ri ìwa-buburu pẹlu, on kò si ni ṣe lãlã lati ṣà a rò. 12 Enia lasan a sa ma fẹ iṣe ọlọgbọ́n, bi a tilẹ ti bi enia bi ọmọ kẹtẹkẹtẹ. 13 Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀. 14 Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ. 15 Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru. 16 Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ. 17 Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀. 18 Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia. 19 Iwọ o si dubulẹ pẹlu kì yio si sí ẹniti yio dẹ̀ruba ọ, ani ọ̀pọ enia yio ma wá oju-rere rẹ. 20 Ṣugbọn oju eniakenia yio mófo, nwọn kì yio le sala, ireti wọn a si dabi ẹniti o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.

Jobu 12

1 JOBU si dahùn o si wipe, 2 Kò si ani-ani nibẹ̀, ṣugbọn ẹnyin li awọn enia na, ọgbọ́n yio si kú pẹlu nyin. 3 Ṣugbọn emi ni iyè ninu gẹgẹ bi ẹnyin: emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani kò mọ̀ nkan bi iru wọnyi? 4 Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà. 5 Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀. 6 Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn. 7 Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ. 8 Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ. 9 Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi? 10 Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye. 11 Eti ki idán ọ̀rọ wò bi? tabi adùn ẹnu ki isi tọ onjẹ rẹ̀ wò? 12 Awọn arugbo li ọgbọ́n wà fun, ati ninu gigùn ọjọ li oye. 13 Pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) li ọgbọ́n ati agbarà, on ni ìmọ ati oye, 14 Kiyesi i, o biwó, a kò si le igbe ró mọ́, o se enia mọ́, kò si sí iṣisilẹ̀ kan. 15 Kiyesi i, o da awọn omi duro, nwọn si gbẹ, o si rán wọn jade, nwọn si ṣẹ bo ilẹ aiye yipo. 16 Pẹlu rẹ̀ li agbara ati ọgbọ́n, ẹniti nṣìna ati ẹniti imu ni ṣìna tirẹ̀ ni nwọn iṣe. 17 O mu awọn igbimọ̀ lọ nihoho, a si sọ awọn onidajọ di wère. 18 O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja. 19 O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá. 20 O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye. 21 O bù ẹ̀gan lu awọn ọmọ-alade, o si tú àmure awọn alagbara. 22 O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀. 23 On a mu orilẹ-ède bi si i, a si run wọn, on a sọ orilẹ-ède di nla, a si tun ṣẹ́ wọn kù. 24 On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si. 25 Nwọn a ma fi ọwọ ta ilẹ ninu òkunkun laisi imọlẹ, on a si ma mu wọn tàse irin bi ọmuti.

Jobu 13

1 Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e. 2 Ohun ti ẹnyin mọ̀, emi mọ̀ pẹlu, emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin. 3 Nitotọ emi o ba Olodumare sọ̀rọ, emi si nfẹ ba Ọlọrun sọ asọye. 4 Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin. 5 O ṣe! ẹ ba kuku pa ẹnu nyin mọ patapata! eyini ni iba si ṣe ọgbọ́n nyin. 6 Ẹ gbọ́ awiye mi nisisiyi, ẹ si fetisilẹ si aroye ẹnu mi. 7 Ẹnyin fẹ sọ isọkusọ fun Ọlọrun? ki ẹ si fi ẹ̀tan sọ̀rọ gbè e? 8 Ẹnyin fẹ ṣojusaju rẹ̀, ẹnyin fẹ igbìjà fun Ọlọrun? 9 O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji. 10 Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ. 11 Iwa ọlá rẹ̀ ki yio bà nyin lẹ̃ru bi? ipaiya rẹ̀ ki yio pá nyin laiya? 12 Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀. 13 Ẹ pa ẹnu nyin mọ kuro lara mi, ki emi ki o le sọ̀rọ, ohun ti mbọ̀ wá iba mi, ki o ma bọ̀. 14 Njẹ nitori kili emi ṣe nfi ehin mi bù ẹran ara mi jẹ, ti mo si gbe ẹmi mi le ara mi lọwọ? 15 Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e, ṣugbọn emi o ma tẹnumọ ọ̀na mi niwaju rẹ̀. 16 Eyi ni yio si ṣe igbala mi pe: àgabagebe kì yio wá siwaju rẹ̀. 17 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi ni ifaiyabalẹ, ati asọpe mi li eti nyin. 18 Wò o nisisiyi emi ti ladi ọ̀ran mi silẹ; emi mọ̀ pe a ó da mi lare. 19 Tani on ti yio ba mi ṣàroye? njẹ nisisiyi, emi fẹ pa ẹnu mi mọ, emi o si jọwọ ẹmi mi lọwọ. 20 Ṣugbọn ọkan ni, máṣe ṣe ohun meji yi si mi, nigbana ni emi kì yio si fi ara mi pamọ, kuro fun ọ, 21 Fa ọwọ rẹ sẹhin kuro lara mi; má si jẹ ki ẹ̀ru rẹ ki o pá mi laiya. 22 Nigbana ni ki iwọ ki o pè, emi o si dahùn, tabi jẹ ki nma sọ̀rọ, ki iwọ ki o si da mi lohùn. 23 Melo li aiṣedede ati ẹ̀ṣẹ mi, mu mi mọ̀ irekọja ati ẹ̀ṣẹ mi! 24 Nitori kini iwọ ṣe pa oju rẹ mọ́, ti o si yàn mi li ọta rẹ? 25 Iwọ o fa ewe ya ti afẹfẹ nfẹ sihin sọhun: iwọ a si ma lepa akemọlẹ poroporo gbigbẹ! 26 Nitoripe iwọ kọwe ohun kikoro si mi, o si mu mi ni aiṣedede ewe mi. 27 Iwọ kàn àba mọ mi lẹsẹ pẹlu, iwọ si nwò ipa ọ̀na irin mi li awofin, iwọ si nfi ãlà yi gigisẹ mi ka. 28 Ani, yi ẹniti a ti run ka, bi ohun ti o bu, bi aṣọ ti kòkoro jẹ bajẹ.

Jobu 14

1 ENIA ti a bi ninu obinrin ọlọjọ diẹ ni, o si kún fun ipọnju. 2 O jade wá bi itana eweko, a si ke e lulẹ, o si nfò lọ bi ojiji, kò si duro pẹ́. 3 Iwọ si nṣiju rẹ wò iru eyinì, iwọ si mu mi wá sinu idajọ pẹlu rẹ. 4 Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan! 5 Njẹ ati pinnu ọjọ rẹ̀, iye oṣu rẹ̀ mbẹ li ọwọ rẹ, iwọ ti pàla rẹ̀, bẹ̃li on kò le ikọja rẹ̀. 6 Yipada kuro lọdọ rẹ̀, ki o le simi titi yio fi pé ọjọ rẹ̀ bi alagbaṣe. 7 Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá. 8 Bi gbongbo rẹ̀ tilẹ di ogbó ninu ilẹ, ti kukute rẹ̀ si kú ni ilẹ. 9 Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko. 10 Ṣugbọn enia kú, a si ṣàn danu; ani enia jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, on ha da? 11 Bi omi ti itán ninu ipa odò, ti odò si ifà ti si igbẹ. 12 Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn. 13 A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ìkọkọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi. 14 Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de. 15 Iwọ iba pè, emi iba si da ọ lohùn, iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ. 16 Ṣugbọn nisisiyi iwọ nkaye iṣisẹ mi, iwọ kò fà ọwọ rẹ kuro nitori ẹ̀ṣẹ mi. 17 A fi edidi di irekọja mi sinu àpo, iwọ si rán aiṣedede mi pọ̀. 18 Ati nitotọ oke nla ti o ṣubu, o dasan, a si ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀. 19 Omi a ma yinrin okuta, iwọ a si mu omi ṣàn bo ohun ti o hù jade lori ilẹ, iwọ si sọ ireti enia di ofo. 20 Iwọ si ṣẹgun rẹ̀ lailai, on si kọja lọ iwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o si ran a lọ kuro. 21 Awọn ọmọ rẹ̀ bọ́ si ipo ọlá, on kò si mọ̀, nwọn si rẹ̀ silẹ, on kò si kiyesi i lara wọn. 22 Ṣugbọn ẹran-ara rẹ̀ ni yio ri irora, ọkàn rẹ̀ ni yio si ma ni ibinujẹ ninu rẹ̀.

Jobu 15

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Keji

1 NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, 2 Ọlọgbọ́n a ma sọ̀rọ ìmọ asan, ki o si ma fi afẹfẹ ila õrùn kún ara rẹ̀ ninu: 3 On le ma fi aroye sọ̀rọ ti kò li ère, tabi pẹlu ọ̀rọ ninu eyiti kò le fi ṣe rere? 4 Ani iwọ ṣa ìbẹru tì, iwọ si dí adura lọna niwaju Ọlọrun. 5 Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò. 6 Ẹnu ara rẹ li o da ọ lẹbi, kì iṣe emi, ani ète ara rẹ li o jẹri tì ọ. 7 Iwọ́ ha iṣe ọkunrin ti a kọ́ bi? tabi a ha dá ọ ṣaju awọn oke? 8 Iwọ gburo aṣiri Ọlọrun ri, tabi iwọ ha dá ọgbọ́n duro sọdọ ara rẹ? 9 Kini iwọ mọ̀ ti awa kò mọ̀, oye kili o ye ọ ti kò si ninu wa. 10 Elewú ogbó ati ògbologbo enia wà pẹlu wa, ti nwọn gbó jù baba rẹ lọ. 11 Itunu Ọlọrun ha kere lọdọ rẹ, ọ̀rọ kan si ṣe jẹjẹ jù lọdọ rẹ. 12 Ẽṣe ti aiya rẹ fi ndà ọ kiri, tabi kini iwọ tẹjumọ wofin. 13 Ti iwọ fi yi ẹmi rẹ pada lodi si Ọlọrun, ti o fi njẹ ki ọ̀rọkọrọ ki o ma bọ li ẹnu rẹ bẹ̃? 14 Kili enia ti o fi mọ́? ati ẹniti a tinu obinrin bi ti yio fi ṣe olododo? 15 Kiyesi i, on (Ọlọrun) kò gbẹkẹle awọn ẹni-mimọ́ rẹ̀, ani awọn ọrun kò mọ́ li oju rẹ̀. 16 Ambọtori enia, ẹni irira ati elẽri, ti nmu ẹ̀ṣẹ bi ẹni mu omi. 17 Emi o fi hàn ọ, gbọ́ ti emi, eyi ti emi si ri, on li emi o si sọ. 18 Ti awọn ọlọgbọ́n ti pa ni ìtan lati ọdọ awọn baba wọn wá, ti nwọn kò si fi pamọ́. 19 Awọn ti a fi ilẹ aiye fun nikan, alejo kan kò si là wọn kọja. 20 Enia buburu nṣe lãlã, pẹlu irora li ọjọ rẹ̀ gbogbo, ati iye ọdun li a dá silẹ fun aninilara. 21 Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i. 22 O kò gbagbọ pe on o jade kuro ninu okunkun; a si ṣa a sapakan fun idà. 23 O nwò kakiri fun onjẹ, wipe, nibo li o wà, o mọ̀ pe ọjọ òkunkun sunmọ tosi. 24 Ipọnju pẹlu irora ọkàn yio mu u bẹ̀ru, nwọn o si ṣẹgun rẹ̀ bi ọba ti imura ogun. 25 Nitoripe o ti nawọ rẹ̀ jade lodi si Ọlọrun, o si mura rẹ̀ le lodi si Olodumare. 26 O sure, o si fi ẹhin giga kọlu u, ani fi ike-koko apata rẹ̀ ti o nipọn. 27 Nitoriti on fi ọra rẹ̀ bo ara rẹ̀ loju, o si ṣe jabajába ọra si ẹgbẹ rẹ̀. 28 On si gbe inu ahoro ilu itakété, ati ninu ileyile ti enia kò gbe mọ́, ti o mura tan lati di àlapa. 29 On kò le ilà, bẹ̃ni ohun ini rẹ̀ kò le iduro pẹ, bẹ̃ni kò le imu pipé rẹ̀ duro pẹ lori aiye. 30 On kì yio jade kuro ninu okunkun, ọ̀wọ-iná ni yio jo ẹká rẹ̀, ati nipasẹ ẹmi ẹnu rẹ̀ ni yio ma kọja lọ kuro. 31 Ki on ki o má ṣe gbẹkẹle asan, o tan ara rẹ̀ jẹ; nitoripe asan ni yio jasi ère rẹ̀. 32 A o mu u ṣẹ ṣaju pipe ọjọ rẹ̀, ẹka rẹ̀ kì yio si tutu. 33 Yio si gbòn talubọ eso rẹ̀ dànu bi àjara, yio si rẹ̀ itana rẹ̀ nù bi ti igi olifi. 34 Nitoripe ajọ awọn àgabagebe yio tuka, iná ni yio si jo agọ abẹtẹlẹ. 35 Nwọn loyun ìwa-ika, nwọn si bi ẹ̀ṣẹ, ikùn wọn si pèse ẹ̀tan.

Jobu 16

1 NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, 2 Emi ti gbọ́ iru ohun pipọ bẹ̃ ri; ayọnilẹnu onitunu enia ni gbogbo nyin. 3 Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn. 4 Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin. 5 Emi iba fi ọ̀rọ ẹnu mi gbà nyin ni iyanju, ati ṣiṣi ète mi iba si tu ibinujẹ nyin. 6 Bi emi tilẹ sọ̀rọ ibinujẹ mi kò rù; bi mo si tilẹ dakẹ, nibo li itunu mi de? 7 Ṣugbọn nisisiyi, o da mi lagara, iwọ (Ọlọrun) mu gbogbo ẹgbẹ mi takete. 8 Iwọ si fi ikiweje kún mi lara, ti o jẹri tì mi; ati rirù ti o yọ lara mi, o jẹri tì mi li oju. 9 Ibinu rẹ̀ li o fà mi ya, o si ṣọta mi; o pa ehin rẹ̀ keke si mi, ọta mi si gboju rẹ̀ si mi. 10 Nwọn ti fi ẹnu wọn yán si mi, nwọn gbá mi li ẹrẹkẹ ni igbá ẹ̀gan, nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si mi. 11 Ọlọrun ti fi mi le ọwọ ẹni-buburu, o si mu mi ṣubu si ọwọ enia ẹlẹṣẹ. 12 Mo ti joko jẹ, ṣugbọn o fa mi já o si dì mi li ọrùn mu, o si gbọ̀n mi tutu, o si gbe mi kalẹ ṣe àmi itasi rẹ̀. 13 Awọn tafatafa rẹ̀ duro yi mi kakiri; o là mi laiya pẹ̀rẹ kò si dasi, o si tú orõrò ara mi dà silẹ. 14 Ibajẹ lori ibajẹ li o fi ba mi jẹ; o sure kọlù mi bi òmirán. 15 Mo rán aṣọ-apo bò ara mi, mo si rẹ̀ iwo mi silẹ ninu erupẹ. 16 Oju mi ti pọ́n fun ẹkún, ojiji ikú si ṣẹ si ipenpeju mi. 17 Kì iṣe nitori aiṣotitọ kan li ọwọ mi, adura mi si mọ́ pẹlu. 18 A! ilẹ aiye, iwọ máṣe bò ẹ̀jẹ mi, ki ẹkún mi máṣe ni ipò kan. 19 Njẹ nisisiyi kiyesi i! ẹlẹri mi mbẹ li ọrun, ẹri mi si mbẹ loke ọrun. 20 Awọn ọre mi nfi mi ṣẹ̀sin, ṣugbọn oju mi ndà omije sọdọ Ọlọrun. 21 Ibaṣepe ẹnikan le ma ṣe alagbawi fun ẹnikeji lọdọ Ọlọrun, bi enia kan ti iṣe alagbawi fun ẹnikeji rẹ̀. 22 Nitori nigbati iye ọdun diẹ rekọja tan, nigbana ni emi o lọ si ibi ti emi kì yio pada bọ̀.

Jobu 17

1 EMI mi bajẹ, ọjọ mi parun, isa-okú duro dè mi. 2 Nitõtọ! awọn ẹlẹya wà lọdọ mi, oju mi si tẹmọ́ imunibinu wọn. 3 Njẹ nisisiyi, fi lelẹ! yàn onigbọwọ fun mi lọdọ rẹ; tani oluwa rẹ̀ ti yio ba mi so ọwọ pọ̀? 4 Nitoripe iwọ ti sé wọn laiya kuro ninu oye, nitorina iwọ kì yio gbé wọn leke. 5 Ẹniti o fi awọn ọrẹ hàn fun igára, on ni oju awọn ọmọ rẹ̀ yio mu ofo. 6 O si sọ mi di ẹni-owe fun awọn enia, niwaju wọn ni mo dabi ẹni itutọ́ si li oju. 7 Oju mi ṣú baibai pẹlu nitori ibinujẹ, gbogbo ẹ̀ya ara mi si dabi ojiji. 8 Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe. 9 Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju. 10 Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin. 11 Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi. 12 A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de. 13 Bi mo tilẹ ni ireti, ipo-okú ni ile mi, mo ti tẹ bùsun mi sinu òkunkun. 14 Emi ti wi fun idibajẹ pe, Iwọ ni baba mi, ati fun kòkoro pe, Iwọ ni iya mi ati arabinrin mi. 15 Ireti mi ha dà nisisiyi? bi o ṣe ti ireti mi ni, tani yio ri i? 16 O sọkalẹ lọ sinu ọgbun ipo-okú, nigbati a jumọ simi pọ̀ ninu erupẹ ilẹ.

Jobu 18

1 NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn o si wipe, 2 Nigba wo li ẹnyin o to fi idi ọ̀rọ tì; ẹ rò o, nigbẹhin rẹ̀ li awa o to ma sọ. 3 Nitori kili a ṣe nkà wa si bi ẹranko, ti a si nkà wa si bi ẹni ẹ̀gan li oju nyin! 4 Iwọ nfa ara rẹ ya pẹrẹpẹrẹ ninu ibinu rẹ, ki a ha kọ̀ aiye silẹ nitori rẹ bi? tabi ki a ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀? 5 Nitotọ imọlẹ enia buburu li a o pa kuro, ọ̀wọ-iná rẹ̀ kì yio si tan imọlẹ: 6 Imọlẹ yio ṣokunkun ninu agọ rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o si pa pẹlu rẹ̀. 7 Irin ẹsẹ agbara rẹ̀ yio di fifọn, ìmọ on tikararẹ ni yio bi i ṣubu. 8 Nipa ẹsẹ on tikararẹ̀ o ti bọ́ sinu àwọn, o si rìn lori okùn didẹ. 9 Okùn ẹgẹ́ ni yio mu u ni gigĩsẹ, awọn igara yio si ṣẹgun rẹ̀. 10 A dẹkùn silẹ fun u lori ilẹ, a si wà ọ̀fin fun u loju ọ̀na. 11 Ẹ̀ru nla yio bà a ni iha gbogbo, yio si le e de ẹsẹ rẹ̀. 12 Ailera rẹ̀ yio di pipa fun ebi, iparun yio dide duro si i ni iha rẹ̀. 13 Yio jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀, akọbi ikú ni yio jẹ agbara rẹ̀ run. 14 Eyi ti o ti gbẹkẹle ni a o fàtu kuro ninu agọ rẹ̀, yio si tọ̀ ọba ẹ̀ru nla nì lọ. 15 Yio si ma joko ninu agọ rẹ̀ eyi ti kì iṣe tirẹ̀, imi-õrùn li a ọ fún kakiri si ara ile rẹ̀. 16 Gbongbo rẹ̀ yio gbẹ nisalẹ, a o si ke ẹ̀ka rẹ̀ kuro loke. 17 Iranti rẹ̀ yio parun kuro li aiye, kì yio si orukọ rẹ̀ ni igboro ilu. 18 A o si le e lati inu imọlẹ sinu òkunkun, a o si le e kuro li aiye. 19 Kì yio ni ọmọ bibikunrin tabi ajọbi-kunrin ninu awọn enia rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o kù ninu agbo ile rẹ̀. 20 Ẹnu yio ya awọn iran ti ìwọ-õrùn si igba ọjọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ru iwariri ti ba awọn iran ti ila-õrùn. 21 Nitõtọ iru-bẹ̃ ni ibujoko awọn enia buburu, eyi si ni ipo ẹni ti kò mọ̀ Ọlọrun.

Jobu 19

1 NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, 2 Yio ti pẹ to ti ẹnyin o fi ma bà mi ninu jẹ, ti ẹnyin o fi ma fi ọ̀rọ kun mi ni ìjanja? 3 Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya. 4 Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami. 5 Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju. 6 Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka. 7 Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ. 8 O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi: 9 O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi. 10 O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi: 11 O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀. 12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka. 13 O mu awọn arakunrin mi jina si mi rére, ati awọn ojulumọ mi di ajeji si mi nitõtọ. 14 Awọn ajọbi mi fà sẹhin, awọn afaramọ́ ọrẹ mi si di onigbagbe mi. 15 Awọn ara inu ile mi ati awọn ọmọbinrin iranṣẹ mi kà mi si ajeji, emi jasi ajeji enia li oju wọn. 16 Mo pè iranṣẹ mi, on kò si da mi lohùn, mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ. 17 Ẹmi mi sú aya mi, ati õrùn mi sú awọn ọmọ inu iya mi. 18 Ani awọn ọmọde fi mi ṣẹsin: mo dide, nwọn si sọ̀rọ ẹ̀gan si mi. 19 Gbogbo awọn ọrẹ idimọpọ mi korira mi, awọn olufẹ mi si kẹ̀hinda mi. 20 Egungun mi lẹ mọ́ awọ ara mi ati mọ́ ẹran ara mi, mo si bọ́ pẹlu awọ ehin mi. 21 Ẹ ṣãnu fun mi, ẹ ṣãnu fun mi, ẹnyin ọrẹ mi, nitori ọwọ Ọlọrun ti bà mi. 22 Nitori kili ẹnyin ṣe lepa mi bi Ọlọrun, ti ẹran ara mi kò tẹ́ nyin lọrùn! 23 A! Ibaṣepe a le kọwe ọ̀rọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe! 24 Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ́ wọn sinu apata fun lailai. 25 Ati emi, emi mọ̀ pe Oludande mi mbẹ li ãyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ. 26 Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun, 27 Ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò, kì si iṣe ti ẹlomiran; ọkàn mi si dáku ni inu mi. 28 Bi ẹnyin ba wipe, Awa o ti lepa rẹ̀ to! ati pe, gbongbo ọ̀rọ na li a sa ri li ọwọ mi, 29 Ki ẹnyin ki o bẹ̀ru idà; nitoripe ibinu ni imu ijiya idà wá: ki ẹnyin ki o lè imọ̀ pe idajọ kan mbẹ.

Jobu 20

1 NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe, 2 Nitorina ni ìro inu mi da mi lohùn, ati nitori eyi na ni mo si yara si gidigidi. 3 Mo ti gbọ́ ẹsan ẹ̀gan mi, ẹmi oye mi si da mi lohùn. 4 Iwọ kò mọ̀ eyi ri ni igba atijọ, lati igba ti a sọ enia lọjọ̀ silẹ aiye? 5 Pe, orin ayọ̀ enia buburu igba kukuru ni, ati pe, ni iṣẹju kan li ayọ̀ àgabagebe. 6 Bi ọlanla rẹ̀ tilẹ goke de ọrun, ti ori rẹ̀ si kan awọsanma. 7 Ṣugbọn yio ṣegbe lailai bi igbẹ́ ara rẹ̀; awọn ti o ti ri i rí, yio wipe, On ha dà? 8 Yio fò lọ bi alá, a kì yio si ri i, ani a o lé e lọ bi iran oru. 9 Oju ti o ti ri i rí pẹlu, kì yio si ri i mọ́, bẹ̃ni ibujoko rẹ̀ kì yio si ri i mọ́. 10 Awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wá ati ri oju-rere lọdọ talaka, ọwọ rẹ̀ yio si kó ẹrù wọn pada. 11 Egungun rẹ̀ kún fun agbara igba ewe rẹ̀, ti yio ba a dubulẹ ninu erupẹ. 12 Bi ìwa buburu tilẹ dùn li ẹnu rẹ̀, bi o tilẹ pa a mọ́ nisalẹ ahọn rẹ̀. 13 Bi o tilẹ dá a si, ti kò si kọ̀ ọ silẹ, ti o pa a mọ sibẹ li ẹnu rẹ̀, 14 Ṣugbọn onjẹ rẹ̀ ninu ikùn rẹ̀ ti yipada, o jasi orõro pamọlẹ ninu rẹ̀; 15 O ti gbe ọrọ̀ mì, yio si tun bì i jade, Ọlọrun yio pọ̀ ọ yọ jade lati inu rẹ̀ wá. 16 O ti fà oró pamọlẹ mu, ahọn gunte ni yio pa a. 17 Kì yio ri odò wọnni, iṣan omi, odò ṣiṣàn oyin ati ti ori amọ́. 18 Ohun ti o ṣíṣẹ fun ni yio mu u pada, kì yio si gbe e mì; gẹgẹ bi ọrọ̀ ti o ni, kì yio si yọ̀ ninu rẹ̀. 19 Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́. 20 Nitori on kò mọ̀ iwa-pẹlẹ ninu ara rẹ̀, ki yio si gbà ninu eyiti ọkàn rẹ̀ fẹ silẹ. 21 Ohun kan kò kù fun jijẹ rẹ̀, nitorina ọrọ̀ rẹ̀ kì yio duro pẹ́. 22 Ninu titó ìkún rẹ̀ yio wà ninu ihale, ọwọ gbogbo awọn oniyọnu ni yio dide si i lori. 23 Yio si ṣe pe, nigbati o ma fi kún inu rẹ̀ yo nì, Ọlọrun yio fa riru ibinu rẹ̀ si i lori, nigbati o ba njẹun lọwọ. 24 Yio sá kuro lọwọ ohun-ogun irin, ọrun akọ-irin ni yio ta a po yọ. 25 O fà a yọ, o si jade kuro lara, ani idà didan ni njade lati inu orõro wá: ẹ̀ru-nla mbẹ li ara rẹ̀. 26 Okunkun gbogbo ni a ti pamọ́ fun iṣura rẹ̀, iná ti a kò fẹ́ ni yio jo o run: yio si jẹ eyi ti o kù ninu agọ rẹ̀ run. 27 Ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ rẹ̀ hàn, aiye yio si dide duro si i. 28 Ibisi ile rẹ̀ yio kọja lọ, ati ohun ini rẹ̀ yio ṣàn danu lọ li ọjọ ibinu Ọlọrun. 29 Eyi ni ipin enia buburu lati ọdọ Ọlọrun wá, ati ogún ti a yàn silẹ fun u lati ọdọ Oluwa wá.

Jobu 21

1 SUGBỌN Jobu dahùn, o si wipe, 2 Ẹ tẹti silẹ dẹdẹ si ohùn mi, ki eyi ki o jasi itunu nyin. 3 Ẹ jọwọ mi ki emi sọ̀rọ, lẹhin igbati mo ba sọ tan, iwọ ma fi ṣẹsin nṣo. 4 Bi o ṣe ti emi ni, aroye mi iṣe si enia bi, tabi ẽtiṣe ti ọkàn mi kì yio fi ṣe aibalẹ? 5 Ẹ wò mi fin, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki ẹ si fi ọwọ le ẹnu nyin. 6 Ani nigbati mo ranti, ẹ̀ru bà mi, iwarìri si mu mi lara. 7 Nitori kini enia buburu fi wà li ãyè, ti nwọn gbọ́, ani ti nwọn di alagbara ni ipa! 8 Iru-ọmọ wọn fi idi kalẹ li oju wọn pẹlu wọn, ati ọmọ-ọmọ wọn li oju wọn. 9 Ile wọn wà laini ewu, bẹ̃ni ọpa-ìna Ọlọrun kò si lara wọn. 10 Akọ-malu wọn a ma gùn, kì isi isé, abomalu wọn a ma bi, ki isi iṣẹnu; 11 Nwọn a ma rán awọn ọmọ wọn wẹwẹ jade bi agbo ẹran, awọn ọmọ wọn a si ma jó. 12 Nwọn mu ohun ọnà orin timbreli ati dùru, nwọn si nyọ̀ si ohùn ifère. 13 Nwọn lo ọjọ wọn ninu ọrọ̀; ni iṣẹjukan nwọn a lọ si ipo-okú. 14 Nitorina ni nwọn ṣe wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa, nitoripe awa kò fẹ ìmọ ipa ọ̀na rẹ! 15 Kini Olodumare ti awa o fi ma sin i? ere kili a o si jẹ bi awa ba gbadura si i! 16 Kiyesi i, alafia wọn kò si nipa ọwọ wọn, ìmọ enia buburu jina si mi rére. 17 Igba melomelo ni a npa fitila enia buburu kú? igba melomelo ni iparun wọn de ba wọn, ti Ọlọrun isi ma pin ibinujẹ ninu ibinu rẹ̀. 18 Nwọn dabi akeku oko niwaju afẹfẹ, ati bi iyangbo, ti ẹfufu-nla fẹ lọ. 19 Ọlọrun to ìya-ẹ̀ṣẹ rẹ̀ jọ fun awọn ọmọ rẹ̀, o san a fun u, yio si mọ̀ ọ. 20 Oju rẹ̀ yio ri iparun ara rẹ̀, yio si ma mu ninu riru ibinu Olodumare. 21 Nitoripe alafia kili o ni ninu ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati a ba ke iye oṣù rẹ̀ kuro li agbedemeji? 22 Ẹnikẹni le ikọ́ Ọlọrun ni ìmọ? on ni sa nṣe idajọ ẹni ibi giga. 23 Ẹnikan a kú ninu pipé agbara rẹ̀, ti o wà ninu irọra ati idakẹ patapata. 24 Ọpọ́n rẹ̀ kún fun omi-ọmú, egungun rẹ̀ si tutu fun ọra. 25 Ẹlomiran a si kú ninu kikoro ọkàn rẹ̀, ti kò si fi inu didun jẹun. 26 Nwọn o dubulẹ bakanna ninu erupẹ, kòkoro yio si ṣùbo wọn. 27 Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi. 28 Nitoriti ẹnyin wipe, nibo ni ile awọn ọmọ alade, ati nibo ni agọ awọn enia buburu nì gbe wà? 29 Ẹnyin kò bere lọwọ awọn ti nkọja lọ li ọ̀na, ẹnyin kò mọ̀ àmi wọn? pe, 30 Enia buburu ni a fi pamọ fun ọjọ iparun, a o si mu wọn jade li ọjọ riru ibinu. 31 Tani yio sọ ipa-ọ̀na rẹ̀ kò o li oju, tani yio si san pada fun u li eyi ti o ti ṣe? 32 Sibẹ a o si sin i li ọ̀na ipo-okú, yio si ma ṣọ́ ororì okú. 33 Ogulutu ọfin yio dùn mọ ọ, gbogbo enia yio si ma tọ̀ ọ lẹhin, bi enia ainiye ti lọ ṣiwaju rẹ̀. 34 E ha ti ṣe ti ẹnyin fi ntù mi ninu lasan! bi o ṣepe ni idahùn nyin eké kù nibẹ.

Jobu 22

ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ KẸTA

1 NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, 2 Enia le iṣe rere fun Ọlọrun, bi ọlọgbọ́n ti iṣe rere fun ara rẹ̀. 3 Ohun ayọ̀ ha ni fun Olodumare pe, olododo ni iwọ? tabi ere ni fun u, ti iwọ mu ọ̀na rẹ pé? 4 Yio ha ba ọ wi bi nitori ìbẹru Ọlọrun rẹ, yio ha ba ọ lọ sinu idajọ bi? 5 Iwa-buburu rẹ kò ha tobi, ati ẹ̀ṣẹ rẹ lainiye? 6 Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn. 7 Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa. 8 Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀. 9 Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́. 10 Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu. 11 Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ? 12 Ọlọrun kò ha jẹ Ẹni giga ọrun? sa wò ori awọn ìrawọ̀ bi nwọn ti ga tó! 13 Iwọ si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀, on ha le iṣe idajọ lati inu awọsanma dudu wá bi? 14 Awọsanma ti o nipọn ni ibora fun u, ti kò fi le riran; o si rin ninu ayika ọrun. 15 Iwọ fẹ rìn ipa-ọ̀na igbani ti awọn enia buburu ti rìn. 16 Ti a ke lulẹ kuro ninu aiye laipé ọjọ wọn, ipilẹ wọn ti de bi odò ṣiṣàn. 17 Awọn ẹniti o wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa! Kini Olodumare yio ṣe fun wọn. 18 Sibẹ o fi ohun rere kún ile wọn! ṣugbọn ìmọ enia-buburu jìna si mi! 19 Awọn olododo ri i, nwọn si yọ̀, awọn alailẹ̀ṣẹ si fi wọn rẹrin ẹlẹya pe: 20 Lotitọ awọn ọta wa ni a ke kuro, iná yio si jó iyokù wọn run. 21 Fa ara rẹ sunmọ Ọlọrun, iwọ o si ri alafia; nipa eyinì rere yio wá ba ọ. 22 Emi bẹ̀ ọ, gba ofin lati ẹnu rẹ̀ wá, ki o si tò ọ̀rọ rẹ̀ si aiya rẹ. 23 Bi iwọ ba yipada sọdọ Olodumare, a si gbe ọ ró, bi iwọ ba si mu ẹ̀ṣẹ jina rére kuro ninu agọ rẹ. 24 Ti iwọ ba tẹ wura daradara silẹ lori erupẹ ati wura ófiri labẹ okuta odò. 25 Nigbana ni Olodumare yio jẹ iṣura rẹ, ani yio si jẹ fadaka fun ọ ni ọ̀pọlọpọ. 26 Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun. 27 Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ. 28 Iwọ si gbimọ ohun kan pẹlu, yio si fi idi mulẹ fun ọ; imọlẹ yio si mọ́ sipa ọ̀na rẹ. 29 Nigbati ipa-ọ̀na rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, Igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ là! 30 Yio gba ẹniti kì iṣe alaijẹbi là, a o si gbà a nipa mimọ́ ọwọ rẹ.

Jobu 23

1 NIGBANA ni Jobu si dahùn wipe, 2 Ani loni ni ọ̀ran mi korò; ọwọ mi si wuwo si ikerora mi. 3 A! emi iba mọ̀ ibi ti emi iba wá Ọlọrun ri! ki emi ki o tọ̀ ọ lọ si ibujoko rẹ̀, 4 Emi iba si tò ọran na niwaju rẹ̀, ẹnu mi iba si kún fun aroye. 5 Emi iba si mọ̀ ọ̀rọ ti on iba fi da mi lohùn, oye ohun ti iba wi a si ye mi. 6 Yio ha fi agbara nla ba mi wijọ bi? agbẹdọ̀! kiki on o si kiyesi mi: 7 Nibẹ li olododo le iba a wijọ, bẹ̃li emi o si bọ́ li ọwọ onidajọ mi lailai. 8 Si wò! bi emi ba lọ si iha ila-õrùn, on kò si nibẹ, ati si iwọ-õrùn ni, emi kò si roye rẹ̀: 9 Niha ariwa bi o ba ṣiṣẹ nibẹ, emi kò ri i, o fi ara rẹ̀ pamọ niha gusu, ti emi kò le ri i. 10 Ṣugbọn on mọ̀ ọ̀na ti emi ntọ̀, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura. 11 Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rẹ, ọ̀na rẹ̀ ni mo ti kiyesi, ti nkò si yà kuro. 12 Bẹ̃ni emi kò pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rẹ̀, emi si pa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ mọ́ jù ofin inu mi lọ. 13 Ṣugbọn oninukan li on, tani yio si yi i pada? Eyiti ọkàn rẹ̀ si ti fẹ, eyi na ni iṣe. 14 Nitõtọ ohun ti ati yàn silẹ fun mi ni nṣe, ọ̀pọlọpọ iru bẹ li o wà li ọwọ rẹ̀. 15 Nitorina ni ara ko ṣe rọ̀ mi niwaju rẹ̀, nigbati mo ba rò o, ẹ̀ru a ba mi. 16 Nitoripe Ọlọrun ti pá mi li aiya, Olodumare si ndamu mi. 17 Nitoriti a kò ti ke mi kuro niwaju òkunkun, bẹ̃ni kò pa òkùnkùn-biribiri mọ kuro niwaju mi.

Jobu 24

1 ẼṢE bi igba-igba kò pamọ lọdọ Olodumare; ti awọn ojulumọ rẹ̀ kò ri ọjọ rẹ̀? 2 Nwọn a ṣi àmi àla ilẹ, nwọn a fi agbara ko agbo ẹran lọ, nwọn si bọ́ wọn. 3 Nwọn a si dà kẹtẹkẹtẹ alainibaba lọ, nwọn a si gba ọdá-malu opó li ohun ògo. 4 Nwọn a bì alaini kuro loju ọ̀na, awọn talaka aiye a sa pamọ́ pọ̀. 5 Kiyesi i, bi kẹtẹkẹtẹ igbẹ ninu ijù ni nwọn ijade lọ si iṣẹ wọn; nwọn a tete dide lati wá ohun ọdẹ; ijù pese onjẹ fun wọn ati fun awọn ọmọ wọn. 6 Olukuluku a si ṣa ọka onjẹ-ẹran rẹ̀ ninu oko, nwọn a si ká ọgba-ajara enia buburu. 7 Nihoho ni nwọn ma sùn laini aṣọ, ti nwọn kò ni ibora ninu otutu. 8 Ọwara ojo oke-nla si pa wọn, nwọn si lẹ̀mọ apata nitoriti kò si abo. 9 Nwọn ja ọmọ-alainibaba kuro li ẹnu-ọmu, nwọn si gbà ohun ẹ̀ri li ọwọ talaka. 10 Nwọn rìn kiri nihoho laili aṣọ, awọn ti ebi npa rẹrù ìdi-ọka. 11 Awọn ẹniti nfún ororo ninu agbala wọn, ti nwọn si ntẹ ifunti àjara, ongbẹ si ngbẹ wọn. 12 Awọn enia nkerora lati ilu wá, ọkàn awọn ẹniti o gbọgbẹ kigbe soke; sibẹ Ọlọrun kò kiyesi iwère na. 13 Awọn li o wà ninu awọn ti o kọ̀ imọlẹ, nwọn kò mọ̀ ipa ọ̀na rẹ̀, bẹni nwọn kò duro nipa ọ̀na rẹ̀. 14 Panipani a dide li afẹmọ́jumọ pa talaka ati alaini, ati li oru a di olè. 15 Oju àlagbere pẹlu duro de ofefe ọjọ, o ni, Oju ẹnikan kì yio ri mi, o si fi iboju boju rẹ̀. 16 Li òkunkun nwọn a runlẹ wọle, ti nwọn ti fi oju sọ fun ara wọn li ọsan, nwọn kò mọ̀ imọlẹ. 17 Nitoripe bi oru dudu ni owurọ̀ fun gbogbo wọn; nitoriti nwọn si mọ̀ ibẹru oru dudu. 18 O yara lọ bi ẹni loju omi; ifibu ni ipin wọn li aiye, on kò rìn lọ mọ li ọ̀na ọgba-ajara. 19 Ọdá ati õru ni imu omi ojo-didi gbẹ, bẹ̃ni isa-okú irun awọn ẹ̀lẹṣẹ. 20 Inu ibímọ yio gbagbe rẹ̀, kokoro ni yio ma fi adun jẹun lara rẹ̀, a kì yio ranti rẹ̀ mọ́; bẹ̃ni a o si ṣẹ ìwa-buburu bi ẹni ṣẹ igi. 21 Ẹniti o hù ìwa-buburu si agàn ti kò bí ri, ti kò ṣe rere si opó. 22 O fi ipá rẹ̀ fà alagbara lọ pẹlu; o dide, kò si ẹniti ẹmi rẹ̀ da loju. 23 On si fi ìwa ailewu fun u, ati ninu eyi ni a o si tì i lẹhin, oju rẹ̀ si wà ni ipa-ọna wọn. 24 A gbe wọn lekè nigba diẹ, nwọn kọja lọ, a si rẹ̀ wọn silẹ, a si mu wọn kuro li ọ̀na, bi awọn ẹlomiran, a si ke wọn kuro bi ori ṣiri itú ọkà bàbà. 25 Njẹ, bi kò ba ri bẹ̃ nisisiyi, tani yio mu mi li eké, ti yio si fi ọ̀rọ mi ṣe alainidi?

Jobu 25

1 NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe, 2 Ijọba ati ẹ̀ru mbẹ lọdọ rẹ̀, on ni iṣe ilaja ni ibi gigagiga rẹ̀. 3 Awọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ni iye bi, tabi ara tani imọlẹ rẹ̀ kò mọ́ si? 4 Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́? 5 Kiyesi i, òṣupa kò si le itan imọlẹ, ani awọn ìrawọ kò mọlẹ li oju rẹ̀. 6 Ambọtori enia ti iṣe idin, ati ọmọ enia, ti iṣe kòkoro!

Jobu 26

1 ṢUGBỌN Jobu si dahùn wipe, 2 Bawo ni iwọ nṣe iranlọwọ ẹniti kò ni ipá, bawo ni iwọ nṣe gbà apa ẹniti kò li agbara? 3 Bawo ni iwọ nṣe ìgbimọ ẹniti kò li ọgbọ́n, tabi bawo ni iwọ nsọdi ọ̀ran li ọ̀pọlọpọ bi o ti ri? 4 Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá? 5 Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀. 6 Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju. 7 On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo. 8 O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn. 9 O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori. 10 O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun. 11 Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀. 12 O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ. 13 Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì. 14 Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀na rẹ̀, ohùn eyiti a gbọ́ ti kere tó! ṣugbọn ãra ipá rẹ̀ tali oye rẹ̀ le iye?

Jobu 27

1 PẸLUPẸLU Jobu si tun sọ kún ọ̀rọ owe rẹ̀ o si wipe, 2 Bi Ọlọrun ti mbẹ ẹniti o gba idajọ mi lọ, ati Olodumare ti o bà mi li ọkàn jẹ. 3 Niwọn igba ti ẹmi mi mbẹ ninu mi, ati ti ẹmi Ọlọrun mbẹ ni iho imú mi. 4 Ete mi kì yio sọ̀rọ eké, bẹ̃li ahọn mi kì yio sọ̀rọ ẹ̀tan. 5 Ki a ma ri pe emi ndá nyin li are, titi emi o fi kú emi kì yio ṣi ìwa otitọ mi kuro lọdọ mi. 6 Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi kì yio si jọwọ rẹ̀ lọwọ; aiya mi kì yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi. 7 Ki ọta mi ki o dàbi enia buburu, ati ẹniti ndide si mi ki o dàbi ẹni alaiṣododo. 8 Nitoripe kini ireti àgabagebe, nigbati Ọlọrun ba ke ẹmi rẹ̀ kuro, nigbati o si fà a jade. 9 Ọlọrun yio ha gbọ́ adura rẹ̀, nigbati ipọnju ba de si i? 10 On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo? 11 Emi o kọ́ nyin li ẹkọ́ niti ọwọ Ọlọrun: eyi ti mbẹ lọdọ Olodumare li emi kì yio fi pamọ. 12 Kiyesi i, gbogbo nyin li o ti ri i, nitori kili ẹnyin ṣe jasi asan pọ̀ bẹ̃? 13 Eyi ni ipín enia buburu lọdọ Ọlọrun, ati ogún awọn aninilara, ti nwọn o gbà lọwọ Olodumare. 14 Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba di pupọ̀, fun idà ni, awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ kì yio yo fun onjẹ. 15 Awọn ti o kù ninu tirẹ̀ li a o sinkú ninu ajakalẹ àrun: awọn opó rẹ̀ kì yio si sọkún. 16 Bi o tilẹ kó fàdaka jọ bi erupẹ, ti o si da aṣọ jọ bi amọ̀. 17 Ki o ma dá a, ṣugbọn awọn olõtọ ni yio lò o; awọn alaiṣẹ̀ ni yio si pin fadaka na. 18 On kọ́ ile rẹ̀ bi kòkoro aṣọ, ati bi agọbukà ti oluṣọ pa. 19 Ọlọrọ̀ yio dubulẹ, ṣugbọn on kì o tùn ṣe bẹ̃ mọ́, o ṣiju rẹ̀, on kò sì si. 20 Ẹ̀ru nla bà a bi omi ṣiṣan, ẹ̀fufu nla ji i gbe lọ li oru. 21 Ẹfufu ila-õrùn gbe e lọ, on si lọ; ati bi iji nla o si fà a kuro ni ipo rẹ̀. 22 Nitoripe Olodumare yio kọlù u, kì o sì dasi; on iba yọ̀ lati sá kuro li ọwọ rẹ̀. 23 Awọn enia yio si ṣapẹ si i lori, nwọn o si ṣe ṣiọ si i kuro ni ipò rẹ̀.

Jobu 28

1 NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura. 2 Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá. 3 Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo. 4 Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia. 5 Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná. 6 Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura. 7 Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri. 8 Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí. 9 O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá. 10 O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo. 11 O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ. 12 Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye? 13 Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè. 14 Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi. 15 A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀. 16 A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. 17 Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀. 18 A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ. 19 Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e. 20 Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? 21 A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. 22 Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. 23 Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, 24 Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. 25 Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. 26 Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: 27 Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. 28 Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!

Jobu 29

Ìparí Ọ̀rọ̀ Jobu

1 PẸLUPẸLU Jobu si tun gbẹnu le ọ̀rọ rẹ̀ o si wipe, 2 A! ibaṣepe emi wà bi igba oṣu ti o kọja, bi ọjọ ti Ọlọrun pa mi mọ́! 3 Nigbati fitila rẹ̀ tàn si mi li ori, ati nipa imọlẹ rẹ̀ emi rìn ninu òkunkun ja. 4 Bi mo ti ri nigba ọ̀dọ́ mi, nigbati aṣiri Ọlọrun wà ninu agọ mi. 5 Nigbati Olodumare wà sibẹ pẹlu mi, nigbati awọn ọmọ mi wà yi mi ka. 6 Nigbati emi nfi ori-amọ wẹ̀ iṣisẹ mi, ati ti apata ntú iṣàn ororo jade fun mi wá. 7 Nigbati mo jade là arin ilu lọ si ẹnu ibode, nigbati mo tẹ ìtẹ mi ni igboro. 8 Nigbana ni awọn ọdọmọkunrin ri mi, nwọn si sapamọ́, awọn àgba dide duro. 9 Awọn ọmọ-alade dakẹ ọ̀rọ sisọ, nwọn a si fi ọwọ wọn le ẹnu. 10 Awọn ọlọla dakẹ, ahọn wọn si lẹmọ èrigi ẹnu wọn. 11 Nitoripe eti gbọ́ ti emi, a si sure fun mi, oju si ri mi, on a jẹri mi. 12 Nitoriti mo gba talaka ti nsọkun, ati alainibaba, ati alaini oluranlọwọ. 13 Isure ẹniti o fẹrẹ iṣegbe wa si ori mi, emi si mu aiya opo kọrin fun ayọ̀. 14 Emi si mu ododo wọ̀, o si bò mi lara; idajọ mi dabi aṣọ igunwa ati ade ọba. 15 Mo ṣe oju fun afọju, ati ẹsẹ̀ fun amọkún. 16 Mo ṣe baba fun talaka, ati ọ̀ran ti emi kò mọ̀, mo wadi rẹ̀ ri. 17 Mo si ká ehin ẹ̀rẹkẹ enia buburu, mo si ja ohun ọdẹ na kuro li ehin rẹ̀. 18 Nigbana ni mo wipe, emi o kú ninu itẹ mi, emi o si mu ọjọ mi pọ̀ si i bi iyanrin. (bi ọjọ ti ẹiyẹ Feniksi.) 19 Gbongbo mi ta lọ si ibi omi, ìri si sẹ̀ si ara ẹká mi titi li oru. 20 Ogo mi gberu lọdọ mi, ọrun mi si pada di titun li ọwọ mi. 21 Emi li enia ndẹti silẹ si, nwọn a si duro, nwọn a si dakẹ ninu ìgbimọ mi. 22 Lẹhin ọ̀rọ mi nwọn kò si tun sọ mọ́, ọ̀rọ mi bọ́ si wọn li eti. 23 Nwọn a si duro dè mi bi ẹnipe fun ojo; nwọn si yanu wọn gboro bi ẹnipe fun ojo àrọ-kuro. 24 Emi si rẹrin si wọn nigbati nwọn kò ba gba a gbọ́; imọlẹ oju mi ni nwọn kò le imu rẹ̀wẹsi. 25 Mo la ọ̀na silẹ fun wọn, mo si joko bi Olu, mo si joko bi ọba ninu ogun, bi ẹniti ntù aṣọ̀fọ̀ ninu.

Jobu 30

1 ṢUGBỌN nisisiyi awọn ti mo gbà li aburo nfi mi ṣẹ̀sin, baba ẹniti emi kẹgàn lati tò pẹlu awọn ajá agbo-ẹran mi. 2 Pẹlupẹlu agbara ọwọ wọn kini o le igbè fun mi, awọn ẹniti kikún ọjọ wọn kò si. 3 Nitori aini ati ìyan nwọn di ẹni itakete, nwọn si girijẹ ohun jijẹ iju, ti o wà ni isọdahoro ati òfo lati lailai. 4 Awọn ẹniti njá ewe-iyọ li ẹ̀ba igbẹ, gbongbo igikigi li ohun jijẹ wọn. 5 A le wọn jade kuro lãrin enia, nwọn si ho le wọn bi ẹnipe si olè. 6 Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta. 7 Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli. 8 Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ. 9 Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn. 10 Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju. 11 Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi. 12 Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi. 13 Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ; 14 Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi. 15 Ẹ̀ru nla yipada bà mi, nwọn lepa ọkàn mi bi ẹfùfù, alafia mi si kọja lọ bi awọsanma. 16 Ati nisisiyi ọkàn mi si dà jade si mi, ọjọ ipọnju dì mi mu. 17 Oru gùn mi ninu egungun mi, eyiti o bù mi jẹ kò si simi. 18 Nipa agbara nla aṣọ mi di pipada, o si lẹmọ́ mi li ara yika bi ọrùn aṣọ ileke mi. 19 O ti mu mi lọ sinu ẹrẹ̀, emi si dabi ekuru ati ẽru, 20 Emi kepè ọ, iwọ kò si gbọ́ ti emi, emi dide duro, iwọ si fi oju lile wò mi. 21 Iwọ pada di ẹni-ìka si mi, ọwọ agbara rẹ ni iwọ fi de ara rẹ li ọ̀na si mi. 22 Iwọ gbe mi soke si ẹ̀fufu, iwọ mu mi fò lọ, bẹ̃ni iwọ si sọ mi di asan patapata. 23 Emi sa mọ̀ pe iwọ o mu mi lọ sinu ikú, ati si ile-apejọ fun gbogbo alãye. 24 Bi o ti wu ki o ṣe, ẹnikan kì yio ha nawọ rẹ̀ ni igba iṣubu rẹ̀, tabi kì yio ké ninu iparun rẹ̀. 25 Emi kò ha sọkun bi fun ẹniti o wà ninu iṣẹ, ọkàn mi kò ha bajẹ fun talaka bi? 26 Nigbati mo fojusọna fun alafia, ibi si de, nigbati emi duro de imọlẹ, òkunkun si de. 27 Ikùn mi nru, kò si simi, ọjọ ipọnju ti bá mi. 28 Emi nṣọ̀fọ lọ rinkiri laisi õrùn, emi dide duro ni awujọ, mo si kigbe. 29 Emi jasi arakunrin ajáko, emi di ẹgbẹ́ awọn abo-ogongo. 30 Àwọ mi di dudu li ara mi, egungun mi si jórun fun õru. 31 Dùru mi pẹlu si di ti ọ̀fọ, ati ohun-ọnà orin mi si di ohùn awọn ti nsọkún.

Jobu 31

1 EMI ti bá oju mi da majẹmu, njẹ emi o ha ṣe tẹjumọ wundia? 2 Nitoripe kini ipin Ọlọrun lati ọrun wá, tabi kini ogún Olodumare lati oke ọrun wá? 3 Kò ṣepe awọn enia buburu ni iparun wà fun, ati ìṣẹniṣẹ fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ? 4 On kò ha ri ipa-ọ̀na mi, on kò ha si ka gbogbo iṣiṣe mi? 5 Bi o ba ṣepe emi ba fi aiṣotitọ rìn, tabi ti ẹsẹ mi si yara si ẹ̀tan. 6 Ki a diwọn mi ninu iwọ̀n ododo, ki Ọlọrun le imọ̀ iduroṣinṣin mi. 7 Bi ẹsẹ mi ba yà kuro loju ọ̀na, ti aiya mi si tẹ̀le ipa oju mi, bi àbawọn kan ba si lẹmọ́ mi li ọwọ. 8 Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu. 9 Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ ibadeni li ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi, 10 Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀. 11 Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ. 12 Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu. 13 Bi mo ba si ṣe aikà ọ̀ran iranṣẹkunrin mi tabi iranṣẹbinrin mi si, nigbati nwọn ba mba mi jà; 14 Kili emi o ha ṣe nigbati Ọlọrun ba dide; nigbati o ba si ṣe ibẹwo, ohùn kili emi o dá? 15 Ẹniti o dá mi ni inu kọ li o da a? ẹnikanna ki o mọ wa ni inu? 16 Bi mo ba fà ọwọ sẹhin fun ifẹ-inu talaka, tabi bi mo ba si mu oju opó mofo; 17 Tabi ti mo ba nikan bu òkele mi jẹ, ti alainibaba kò jẹ ninu rẹ̀; 18 Nitoripe lati igba ewe mi wá li a ti tọ́ ọ dàgba pẹlu mi bi ẹnipe baba, emi si nṣe itọju rẹ̀ (opó) lati inu iya mi wá. 19 Bi emi ba ri olupọnju laini aṣọ, tabi talaka kan laini ibora; 20 Bi ẹgbẹ rẹ̀ kò ba sure fun mi, tabi bi ara rẹ̀ kò si gbona nipasẹ irun agutan mi. 21 Bi mo ba si gbe ọwọ mi soke si alainibaba, nitoripe mo ri iranlọwọ mi li ẹnu-bode, 22 Njẹ ki apá mi ki o wọ́n kuro li ọkọ́ ejika rẹ̀, ki apá mi ki o si ṣẹ́ lati egungun rẹ̀ wá. 23 Nitoripe iparun lati ọdọ Ọlọrun wá ni ẹ̀ru-nla fun mi, ati nitori Ọlanla rẹ̀ emi kò le iduro. 24 Bi o ba ṣepe mo fi wura ṣe igbẹkẹle mi, tabi bi mo ba wi fun wura didara pe, iwọ ni igbẹkẹle mi; 25 Bi mo ba yọ̀ nitori ọrọ̀ mi pọ̀, ati nitori ọwọ mi dẹ̀ lọpọlọpọ; 26 Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ, 27 Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi: 28 Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke. 29 Bi o ba ṣepe mo yọ̀ si iparun ẹniti o korira mi, tabi bi mo ba si gbera soke, nigbati ibi bá a. 30 Bẹ̃li emi kò si jẹ ki ẹnu mi ki o ṣẹ̀ nipa fifẹ egún si ọkàn rẹ̀. 31 Bi awọn enia inu agọ mi kò ba le wipe, Tali o le ri ẹniti agbo-ẹran rẹ̀ kò tẹlọrùn? 32 Alejo kò wọ̀ ni igboro ri, emi ṣi ilẹkun mi silẹ fun èro. 33 Bi mo ba bò irekọja mi mọlẹ bi Adamu, ni pipa ẹbi mi mọ́ li aiya mi: 34 Ọ̀pọlọpọ enia ni mo ha bẹ̀ru bi, tabi ẹ̀gan awọn idile ni mba mi li ẹ̀ru? ti mo fi pa ẹnu mọ́, ti emi kò si fi jade sode? 35 Ibaṣepe ẹnikan le gbọ́ ti emi! kiyesi i, àmi mi! ki Olodumare ki o da mi lohùn! ki emi ki o si ri iwe na ti ọta mi ti kọ! 36 Nitõtọ emi iba gbe e le ejika mi, emi iba si dì i bi ade mọ́ ori mi. 37 Emi iba si sọ iye ìṣisẹ mi fun u, bi ọmọ-alade li emi iba sunmọ ọdọ rẹ̀. 38 Bi ilẹ mi ba si ke fi mi sùn, tabi ti aporo rẹ̀ pẹlu si sọkun, 39 Bi mo ba jẹ eso oko mi lainawo si i, tabi ti mo si mu ọkàn oluwa rẹ̀ fò lọ, 40 Ki ẹgun òṣuṣu ki o hù nipo alikama, ati wèpe nipo ọka-bàba. (Ọ̀rọ Jobu pari.)

Jobu 32

Ọ̀rọ̀ Elihu

1 BẸ̃NI awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi dakẹ lati da Jobu lohùn, nitori o ṣe olododo loju ara rẹ̀. 2 Nigbana ni inu bi Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, lati ibatan idile Ramu; o binu si Jobu, nitoriti o da ara rẹ̀ lare kàka ki o da Ọlọrun lare. 3 Inu rẹ̀ si bi si awọn ọ̀rẹ rẹ̀ mẹtẹta, nitoriti nwọn kò ni idahùn, bẹ̃ni nwọn dá Jobu lẹbi. 4 Njẹ Elihu ti duro titi Jobu fi sọ̀rọ tan, nitoriti awọn wọnyi dàgba jù on lọ ni iye ọjọ. 5 Nigbati Elihu ri pe idahùn ọ̀rọ kò si li ẹnu awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, nigbana ni o binu. 6 Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin. 7 Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n. 8 Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye. 9 Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye. 10 Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn. 11 Kiyesi i, emi ti duro de ọ̀rọ nyin, emi fetisi aroye nyin, nigbati ẹnyin nwá ọ̀rọ ti ẹnyin o sọ. 12 Ani mo fiyesi nyin tinutinu, si kiyesi i, kò si ẹnikan ninu nyin ti o le já Jobu li irọ́, tabi ti o lè ida a lohùn ọ̀rọ rẹ̀! 13 Ki ẹnyin ki o má ba wipe, awa wá ọgbọ́n li awari: Ọlọrun li o lè bi i ṣubu, kì iṣe enia. 14 Bi on kò ti sọ̀rọ si mi, bẹ̃li emi kì yio fi ọ̀rọ nyin da a lohùn. 15 Ẹnu si yà wọn, nwọn kò si dahùn mọ́, nwọn ṣiwọ ọ̀rọ isọ. 16 Mo si reti, nitoriti nwọn kò si fọhùn, nwọn dakẹ jẹ, nwọn kò si dahùn mọ́. 17 Bẹ̃li emi o si dahùn nipa ti emi, emi pẹlu yio si fi ìmọ mi hàn. 18 Nitoripe emi kún fun ọ̀rọ sisọ, ẹmi nrọ̀ mi ni inu mi. 19 Kiyesi i, ikùn mi dabi ọti-waini, ti kò ni oju-iho; o mura tan lati bẹ́ bi igo-awọ titun. 20 Emi o sọ, ki ara ki o le rọ̀ mi, emi o ṣi ète mi, emi o si dahùn. 21 Lotitọ emi kì yio ṣe ojusaju enia, bẹ̃li emi kì yio si ṣe ipọnni fun ẹnikan. 22 Nitoripe emi kò mọ̀ ọ̀rọ ipọnni sọ, ni ṣiṣe bẹ̃ Ẹlẹda mi yio mu mi kuro lọgan.

Jobu 33

1 NJẸ nitorina, Jobu, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ mi, ki o si fetisi ọ̀rọ mi! 2 Kiyesi i nisisiyi, emi ya ẹnu mi, ahọn mi si sọ̀rọ li ẹnu mi. 3 Ọ̀rọ mi yio si jasi iduroṣinṣin ọkàn mi, ete mi yio si sọ ìmọ mi jade dajudaju. 4 Ẹmi Ọlọrun li o ti da mi, ati imisi Olodumare li o ti fun mi ni ìye. 5 Bi iwọ ba le da mi lohùn, tò ọ̀rọ rẹ lẹsẹsẹ niwaju mi, dide duro! 6 Kiyesi i, bi iwọ jẹ ti Ọlọrun, bẹ̃li emi na; lati erupẹ wá ni a si ti dá mi pẹlu. 7 Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara. 8 Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe, 9 Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi. 10 Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀. 11 O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo. 12 Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ! 13 Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀? 14 Nitoripe Ọlọrun sọ̀rọ lẹkan, ani lẹkeji ṣugbọn enia kò roye rẹ̀. 15 Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun. 16 Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn. 17 Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia. 18 O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà. 19 A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a. 20 Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn. 21 Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade. 22 Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú. 23 Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni: 24 Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada! 25 Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀. 26 O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia. 27 O bojuwo enia, bi ẹnikan ba si wipe, Emi ṣẹ̀, mo si ti yi eyi ti o tọ́ po, a kò si sẹsan rẹ̀ fun mi; 28 O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ! 29 Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta, 30 Lati mu ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu ihò, lati fi imọlẹ alãyè mọ́ si i. 31 Jobu! kiyesi i gidigidi, ki o si fetisilẹ si mi; pa ẹnu rẹ mọ́, emi o si ma sọ! 32 Bi iwọ ba si ni ohun iwi, da mi lohùn, mã sọ, nitoripe emi nfẹ da ọ lare. 33 Bi bẹ̃ kọ̀, gbọ temi, pa ẹnu rẹ mọ́; emi o si kọ́ ọ li ọgbọ́n.

Jobu 34

1 PẸLUPẸLU Elihu dahùn o si wipe, 2 Ẹnyin ọlọgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi, ki ẹ si dẹtisilẹ si mi, ẹnyin ti ẹ ni ìmoye. 3 Nitoripe eti a ma dán ọ̀rọ wò, bi adùn ẹnu ti itọ onjẹ wò. 4 Ẹ jẹ ki a ṣà idajọ yàn fun ara wa; ẹ jẹ ki a mọ̀ ohun ti o dara larin wa. 5 Nitoripe Jobu wipe, Olododo li emi; Ọlọrun si ti gbà idajọ mi lọ. 6 Emi ha lè ipurọ si itọsí mi bi, ọfa mi kò ni awọtan, laiṣẹ ni. 7 Ọkunrin wo li o dabi Jobu, ti nmu ẹ̀gan bi ẹni mu omi. 8 Ti mba awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ kẹgbẹ, ti o si mba awọn enia buburu rin. 9 Nitori o sa ti wipe, Ère kan kò si fun enia, ti yio fi ma ṣe inu didun si Ọlọrun, 10 Njẹ nitorina, ẹ fetisilẹ si mi, ẹnyin enia amoye: odõdi fun Ọlọrun ti iba fi huwa buburu, ati fun Olodumare, ti yio fi ṣe aiṣedede! 11 Nitoripe ẹsan iṣẹ enia ni yio san fun u, yio si mu olukuluku ki o ri gẹgẹ bi ipa-ọ̀na rẹ̀. 12 Nitõtọ Ọlọrun kì yio hùwakiwa, bẹ̃ni Olodumare kì yio yi idajọ po. 13 Tani o fi itọju aiye lé e lọwọ, tabi tali o to gbogbo aiye lẹsẹlẹsẹ? 14 Bi o ba gbe aiya rẹ̀ le kiki ara rẹ̀, ti o si gba ọkàn rẹ̀ ati ẹmi rẹ̀ sọdọ ara rẹ̀, 15 Gbogbo enia ni yio parun pọ̀, enia a si tun pada di erupẹ. 16 Njẹ nisisiyi, bi iwọ ba ni oye, gbọ́ eyi, fetisi ohùn ẹnu mi. 17 Ẹniti o korira otitọ le iṣe olori bi? iwọ o ha si da olõtọ-ntọ̀ lẹbi? 18 O ha tọ́ lati wi fun ọba pe, Enia buburu ni iwọ, tabi fun awọn ọmọ-alade pe, Alaimọ-lọrun li ẹnyin? 19 Ambọtori fun ẹniti kì iṣojuṣaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ̀ si jù talaka lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ̀ ni gbogbo wọn iṣe. 20 Ni iṣẹju kan ni nwọn o kú, awọn enia a si di yiyọ lẹnu larin ọganjọ, nwọn a si kọja lọ; a si mu awọn alagbara kuro laifi ọwọ́ ṣe. 21 Nitoripe oju rẹ̀ mbẹ ni ipa-ọ̀na enia, on si ri irin rẹ̀ gbogbo. 22 Kò si òkunkun, tabi ojiji ikú, nibiti awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio gbe sapamọ si. 23 Nitoripe on kò pẹ ati kiyesi ẹnikan, ki on ki o si mu u lọ sinu idajọ niwaju Ọlọrun. 24 On o fọ awọn alagbara tútu laini-iwadi, a si fi ẹlomiran dipo wọn, 25 Nitoripe o mọ̀ iṣẹ wọn, o si yi wọn po di oru, bẹ̃ni nwọn di itẹrẹ́ pọ̀. 26 O kọlu wọn bi enia buburu, nibiti awọn ẹlomiran ri i. 27 Nitorina ni nwọn pada kẹhinda si i, nwọn kò si ti fiyesi ipa-ọ̀na rẹ̀ gbogbo. 28 Ki nwọn ki o si mu igbe ẹkún awọn talaka lọ de ọdọ rẹ̀, on si gbọ́ igbe ẹkún olupọnju. 29 Nigbati o ba fun ni ni irọra, tani yio da a lẹbi, nigbati o ba pa oju rẹ̀ mọ, tani yio le iri i? bẹ̃ni o ṣe e si orilẹ-ède tabi si enia kanṣoṣo. 30 Ki agabagebe ki o má ba jọba, ki nwọn ki o má di idẹwo fun enia. 31 Nitoripe ẹnikan ha le wi fun Ọlọrun pe, emi jiya laiṣẹ̀? 32 Eyi ti emi kò ri, iwọ fi kọ́ mi, bi mo ba si dẹṣẹ, emi kì yio ṣe bẹ̃ mọ́. 33 Iṣe bi ti inu rẹ pe, on o san ẹ̀san pada? njẹ on yio san a pada, iwọ iba kọ̀ ọ tabi iwọ iba fẹ ẹ, kì iṣe emi, pẹlupẹlu kili iwọ mọ̀, sọ ọ! 34 Awọn enia amoye yio wi fun mi, ati pẹlupẹlu ẹnikẹni ti nṣe ọlọgbọ́n, ti o si gbọ́ mi. 35 Jobu ti fi aimọ̀ sọ̀rọ, ọ̀rọ rẹ̀ si ṣe alaigbọ́n. 36 Ifẹ mi ni ki a dán Jobu wò de opin, nitori idahùn rẹ̀ nipa ọ̀na enia buburu; 37 Nitoripe o fi iṣọtẹ kún ẹ̀ṣẹ rẹ̀, o papẹ́ li awujọ wa, o si sọ ọ̀rọ pupọ si Ọlọrun.

Jobu 35

1 ELIHU sọ pẹlu o si wipe, 2 Iwọ rò pe eyi ha tọ́, ti iwọ wipe, ododo mi ni eyi niwaju Ọlọrun pe, 3 Nitoriti iwọ wipe, Ère kini yio jasi fun ọ, tabi ère kili emi o fi jẹ jù ère ẹ̀ṣẹ mi lọ? 4 Emi o da ọ lohùn ati awọn ẹgbẹ rẹ pẹlu rẹ. 5 Ṣiju wò ọrun, ki o ri i, ki o si bojuwo awọsanma ti o ga jù ọ lọ. 6 Bi iwọ ba ṣẹ̀ kini iwọ fi ṣe si i? tabi bi irekọja rẹ di pupọ, kini iwọ fi eyini ṣe si i? 7 Bi iwọ ba si ṣe olododo, kini iwọ fi bùn u, tabi kili on ri gbà lati ọwọ rẹ wá? 8 Ìwa buburu rẹ ni fun enia bi iwọ; ododo rẹ si ni fun ọmọ enia. 9 Nipa ọ̀pọlọpọ ininilara nwọn mu ni kigbe, nwọn kigbe nitori apá awọn alagbara. 10 Ṣugbọn kò si ẹniti o wipe, Nibo ni Ọlọrun Ẹlẹda mi wà, ti o fi orin fun mi li oru? 11 Ti on kọ́ wa li ẹkọ́ jù awọn ẹranko aiye lọ, ti o si mu wa gbọ́n jù awọn ẹiyẹ oju ọrun lọ. 12 Nigbana ni nwọn ke, ṣugbọn Ọlọrun kò dahùn nitori igberaga awọn enia buburu. 13 Nitõtọ Ọlọrun kì yio gbọ́ asan, bẹ̃ni Olodumare kì yio kà a si. 14 Bi o tilẹ ṣepe iwọ wipe, iwọ kì iri i, ọran idajọ mbẹ niwaju rẹ̀, ẹniti iwọ si gbẹkẹle. 15 Ṣugbọn nisisiyi nitoriti ibinu rẹ̀ kò ti ṣẹ́ ọ niṣẹ, on kò ha le imọ̀ ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ bi? 16 Nitorina ni Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀ lasan, o sọ ọ̀rọ di pupọ laisi ìmọ.

Jobu 36

1 ELIHU si sọ si i lọ wipe, 2 Bùn mi laye diẹ, emi o si fi hàn ọ, nitori ọ̀rọ sisọ ni o kù fun Ọlọrun. 3 Emi o mu ìmọ mi ti ọ̀na jijin wá, emi o si fi ododo fun Ẹlẹda mi. 4 Nitoripe ọ̀rọ mi kì yio ṣeke nitõtọ, ẹniti o pé ni ìmọ wà pẹlu rẹ. 5 Kiyesi i, Ọlọrun li agbara, kò si gàn ẹnikẹni, o li agbara ni ipá ati oye. 6 On kì ida ẹmi enia buburu sí, ṣugbọn o fi otitọ fun awọn talaka. 7 On kì imu oju rẹ̀ kuro lara olododo, ṣugbọn pẹlu awọn ọba ni nwọn wà lori itẹ; ani o fi idi wọn mulẹ lailai, a si gbe wọn lekè. 8 Bi a ba si dè wọn ninu àba, ti a si fi okun ipọnju dè wọn, 9 Nigbana ni ifi iṣẹ wọn hàn fun wọn, ati irekọja wọn ti nwọn fi gbe ara wọn ga. 10 O ṣi wọn leti pẹlu si ọ̀na ẹkọ́, o si paṣẹ ki nwọn ki o pada kuro ninu aiṣedede. 11 Bi nwọn ba gbagbọ, ti nwọn si sin i, nwọn o lò ọjọ wọn ninu ìrọra, ati ọdun wọn ninu afẹ́. 12 Ṣugbọn bi nwọn kò ba gbagbọ, nwọn o ti ọwọ idà ṣègbe, nwọn a si kú laini oye. 13 Ṣugbọn awọn àgabagebe li aiya kó ibinu jọ; nwọn kò kigbe nigbati o ba dè wọn. 14 Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu. 15 On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara. 16 Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra. 17 Ṣugbọn iwọ kún fun idajọ awọn enia buburu; idajọ ati otitọ di ọ mu. 18 Nitori ibinu mbẹ, ṣọra ki titó rẹ ma bà tàn ọ lọ; má si ṣe jẹ ki titobi irapada mu ọ ṣìna. 19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ to, ti wahala kì yio fi de ba ọ bi? tabi ipá agbara rẹ? 20 Má ṣe ifẹ oru, nigbati a nke awọn orilẹ-ède kuro ni ipo wọn. 21 Ma ṣọra ki iwọ ki o má yi ara rẹ pada si asan, nitori eyi ni iwọ ti ṣàyan jù sũru lọ. 22 Kiyesi i, Ọlọrun a gbeni ga nipa agbara rẹ̀, tani jẹ olukọni bi on? 23 Tali o là ọ̀na-iṣẹ rẹ̀ silẹ fun u, tabi tali o lè wipe, Iwọ ti nṣe aiṣedede? 24 Ranti ki iwọ ki o gbe iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti enia ima kọrin si. 25 Olukuluku enia a ma ri i, ẹni-ikú a ma wò o li okere. 26 Kiyesi i, Ọlọrun tobi, awa kò si mọ̀ bi o ti tobi to! bẹ̃ni a kò le wadi iye ọdun rẹ̀ ri. 27 Nitoripe on li o fa ikán omi ojo silẹ, ki nwọn ki o kán bi ojo ni ikuku rẹ̀. 28 Ti awọsanma nrọ̀, ti o si nfi sẹ̀ lọpọlọpọ lori enia. 29 Pẹlupẹlu ẹnikẹni le imọ̀ itanká awọsanma, tabi ariwo agọ rẹ̀? 30 Kiyesi i, o tàn imọlẹ yi ara rẹ̀ ka, o si fi isalẹ omi okun bò ara rẹ̀ mọlẹ. 31 Nitoripe nipa wọn ni nṣe idajọ enia, o fun ni li onjẹ li ọ̀pọlọpọ. 32 O fi imọlẹ̀ bò ọwọ rẹ̀ mejeji, o si ran a si ẹni olodi. 33 Ariwo ãrá rẹ̀ fi i han ni, ọ̀wọ-ẹran pẹlu wipe, O sunmọ etile!

Jobu 37

1 AIYA si fò mi si eyi pẹlu, o si ṣi kuro ni ipò rẹ̀. 2 Fetisilẹ dãda, ki ẹ si gbọ́ iró ohùn rẹ̀, ati iró ti o ti ẹnu rẹ̀ jade wá. 3 O ṣe ilana rẹ̀ nisalẹ abẹ ọrun gbogbo, manamana rẹ̀ ni o si jọwọ rẹ̀ lọwọ de opin ilẹ aiye. 4 Lẹhin manamana ohùn kan fọ̀ ramuramu, o fi ohùn ọlanla rẹ̀ sán ãrá: on kì yio si da ãrá duro nigbati a ba ngbọ́ ohùn rẹ̀. 5 Ọlọrun fi ohùn rẹ̀ sán ãrá iyanilẹnu, ohun nlanla ni iṣe ti awa kò le imọ̀. 6 Nitoriti o wi fun ojo didì pe, Iwọ rọ̀ silẹ aiye, ati pẹlu fun ọwọ ojo, ati fun ojo nla agbara rẹ̀. 7 O fi edidi di gbogbo enia, ki gbogbo wọn ki o le imọ̀ iṣẹ rẹ̀. 8 Nigbana ni awọn ẹranko iwọnu ihò lọ, nwọn a si wà ni ipò wọn. 9 Lati iha gusu ni ìji ajayika ti ijade wá, ati otutu lati inu afẹfẹ ti tu awọsanma ká. 10 Nipa ẹmi Ọlọrun a fi ìdi-omi funni, ibu-omi a si sunkì. 11 Pẹlupẹlu o fi omi pupọ mu awọsanma wuwo, a si tú awọsanma imọlẹ rẹ̀ ká. 12 Awọn wọnyi ni a si yi kakiri nipa ilana rẹ̀, ki nwọn ki o le iṣe ohunkohun ti o pa fun wọn li aṣẹ loju aiye lori ilẹ. 13 O mu u wá ibãṣe fun ikilọ̀ ni, tabi fun rere ilẹ rẹ̀, tabi fun ãnu. 14 Jobu dẹtisilẹ si eyi, duro jẹ, ki o si rò iṣẹ iyanu Ọlọrun. 15 Iwọ mọ̀ akoko ìgba ti Ọlọrun sọ wọn lọjọ̀, ti o si mu imọlẹ awọsanma rẹ̀ dán? 16 Iwọ mọ̀ ọ̀na ti awọsanma ifo lọ; iṣẹ iyanu ẹniti o pé ni ìmọ? 17 Aṣọ rẹ̀ ti ma gbona, nigbati o mu aiye dakẹ lati gusu wá. 18 Iwọ ha ba a tẹ pẹpẹ oju-ọrun, ti o duro ṣinṣin, ti o si dabi digi ti o yọ́ dà. 19 Kọ́ wa li eyi ti a le iwi fun u; nitoripe awa kò le iladi ọ̀rọ nitori òkunkun. 20 A o ha wi fun u pe, Emi fẹ sọ̀rọ? tabi ẹnikan wipe, Ifẹ mi ni pe ki a gbe mi mì? 21 Sibẹ nisisiyi enia kò ri imọlẹ ti ndán ninu awọsanma, ṣugbọn afẹfẹ kọja, a si gbá wọn mọ́. 22 Wura didan ti inu iha ariwa jade wá, lọdọ Ọlọrun li ọlanla ẹ̀ru-nla. 23 Nipa ti Olodumare awa kò le iwadi rẹ̀ ri, o rekọja ni ipá, on kì iba idajọ ati ọ̀pọlọpọ otitọ jẹ. 24 Nitorina enia a ma bẹ̀ru rẹ̀, on kì iṣojusaju ẹnikẹni ti o gbọ́n ni inu.

Jobu 38

OLUWA dá Jobu Lóhùn

1 NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe, 2 Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun. 3 Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn. 4 Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye! 5 Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀. 6 Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ? 7 Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀? 8 Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá? 9 Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀? 10 Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun. 11 Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ. 12 Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀? 13 Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀. 14 Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa. 15 A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́. 16 Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla? 17 A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú? 18 Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀? 19 Ọ̀na wo ni imọlẹ igbé, bi o ṣe ti òkunkun, nibo ni ipò rẹ̀? 20 Ti iwọ o fi mu u lọ si ibi àla rẹ̀, ti iwọ o si le imọ̀ ipa-ọ̀na lọ sinu ile rẹ̀? 21 Iwọ mọ̀ eyi, nitoriti ni igbana ni a bi ọ? ati iye ọjọ rẹ si pọ! 22 Iwọ ha wọ inu iṣura ojò-dídì lọ ri bí, iwọ si ri ile iṣura yinyin ri? 23 Ti mo ti fi pamọ de igba iyọnu, de ọjọ ogun ati ijà. 24 Ọ̀na wo ni imọlẹ fi nyà, ti afẹfẹ ila-orun tàn kakiri lori ilẹ aiye? 25 Tali o la ipado fun ẹkún iṣan omi, ati ọ̀na fun manamana ãrá? 26 Lati mu u rọ̀jo sori aiye, nibiti enia kò si, ni aginju nibiti enia kò si. 27 Lati mu ilẹ tutù, ijù ati alairo, ati lati mu irudi ọmudún eweko ru jade? 28 Ojo ha ni baba bi, tabi tali o bi ikán ìsẹ-iri? 29 Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i? 30 Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀. 31 Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu? 32 Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Massaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀? 33 Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye? 34 Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ? 35 Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ! 36 Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya? 37 Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade. 38 Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀? 39 Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun? 40 Nigbati nwọn ba mọlẹ ninu iho wọn, ti nwọn si ba ni ibuba de ohun ọdẹ. 41 Tani npese ohun jijẹ fun ìwo? nigbati awọn ọmọ rẹ̀ nkepe Ọlọrun, nwọn a ma fò kiri nitori aili ohun jijẹ.

Jobu 39

1 IWỌ mọ̀ akoko igbati awọn ewurẹ ori apata ibimọ, iwọ si le ikiyesi igba ti abo-agbọnrin ibimọ? 2 Iwọ le ika iye oṣu ti nwọn npé, iwọ si mọ̀ àkoko igba ti nwọn ibi? 3 Nwọn tẹ ara wọn ba, nwọn bimọ wọn, nwọn si mu ikãnu wọn jade. 4 Awọn ọmọ wọn ri daradara, nwọn dagba ninu ọ̀dan, nwọn jade lọ, nwọn kò si tun pada wá mọ́ sọdọ wọn. 5 Tali o jọ̃ kẹtẹkẹtẹ-oko lọwọ, tabi tali o tú ide kẹtẹkẹtẹ igbẹ́? 6 Eyi ti mo fi aginju ṣe ile fun, ati ilẹ iyọ̀ ni ibugbe rẹ̀. 7 O rẹrin si ariwo ilu, bẹ̃ni on kò si gbọ́ igbe darandaran. 8 Ori àtòle oke-nla ni ibujẹ oko rẹ̀, on a si ma wá ewe tutu gbogbo ri. 9 Agbanrere ha jẹ sìn ọ bi, tabi o jẹ duro ni ibujẹ ẹran rẹ? 10 Iwọ le ifi kátà dè agbanrere ninu aporo, tabi o jẹ ma fà itulẹ ninu aporo oko tọ̀ ọ lẹhin? 11 Iwọ o gbẹkẹlẹ e, nitori agbara rẹ̀ pọ̀, iwọ o si fi iṣẹ rẹ le e li ọwọ? 12 Iwọ le igbẹkẹle e pe, yio mu eso oko rẹ wá sile; pe, yio si ko o jọ sinu àka rẹ̀? 13 Iyẹ abo-ogongo nfi ayọ̀ fì, iyẹ ati ihuhu rẹ̀ daradara ni bi? 14 Kò ri bẹ̃? o fi ẹyin rẹ̀ silẹ-yilẹ, a si mu wọn gbona ninu ekuru. 15 Ti o si gbagbe pe, ẹsẹ le itẹ wọn fọ, tabi pe, ẹranko igbẹ le itẹ wọn fọ: 16 Kò ni ãjo si awọn ọmọ rẹ̀ bi ẹnipe nwọn kì iṣe tirẹ̀, asan ni iṣẹ rẹ̀ laibẹru: 17 Nitoripe Ọlọrun dù u li ọgbọ́n, bẹ̃ni kò si fi ipin oye fun u. 18 Nigbati o gbe ara soke, o gàn ẹṣin ati ẹlẹṣin. 19 Iwọ li o fi agbara fun ẹṣin, iwọ li o fi gọ̀gọ wọ ọrùn rẹ̀ li aṣọ? 20 Iwọ le imu u fò soke bi ẹlẹnga, ogo ẽmi imu rẹ̀ ni ẹ̀ru-nla. 21 O fi ẹsẹ halẹ ninu aporo, o si yọ̀ si agbara rẹ̀; o nlọ jade lati pade awọn ahamọra ogun. 22 O fi oju kekere wò ẹ̀ru, aiya kò si fò o; bẹ̃ni kì isi ipada sẹhin kuro lọwọ idà. 23 Lọdọ rẹ̀ ni apo-ọfa nmi pẹkẹpẹkẹ, ati ọ̀kọ didan ati apata. 24 On fi kikoro oju ati ibinu nla gbe ilẹ mì, bẹ̃li on kò si gbagbọ pe, iro ipè ni. 25 O wi ni igba ipè pe, Ha! Ha! o si gborùn ogun lokere rere: ãrá awọn balogun ati ihó àyọ wọn. 26 Awodi a ma ti ipa ọgbọ́n rẹ fò soke, ti o si nà iyẹ apa rẹ̀ siha gusu? 27 Idì a ma fi aṣẹ rẹ fò lọ soke, ki o si lọ itẹ ìtẹ rẹ̀ si oke giga? 28 O ngbe o si wọ̀ li ori apata, lori palapala okuta ati ibi ori oke. 29 Lati ibẹ lọ ni ima wá ọdẹ kiri, oju rẹ̀ si riran li òkere rere. 30 Awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu a ma mu ẹ̀jẹ, nibiti okú ba gbe wà, nibẹ li on wà pẹlu.

Jobu 40

1 OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe, 2 Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn! 3 Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe: 4 Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi. 5 Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́. 6 Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: 7 Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. 8 Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? 9 Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on? 10 Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ. 11 Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ. 12 Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn. 13 Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ. 14 Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la. 15 Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu. 16 Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀. 17 On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀. 18 Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin. 19 On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ. 20 Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire. 21 O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ. 22 Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri. 23 Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀. 24 Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀?

Jobu 41

1 IWỌ le ifi ìwọ fa Lefiatani [ọni nla] jade, tabi iwọ le imu ahọn rẹ̀ ninu okùn? 2 Iwọ le ifi ìwọ bọ̀ ọ ni imu, tabi o le ifi ẹgun lu u li ẹrẹkẹ? 3 On o ha jẹ bẹ ẹ̀bẹ lọdọ rẹ li ọ̀pọlọpọ bi, on o ha ba ọ sọ̀rọ pẹlẹ? 4 On o ha ba ọ dá majẹmu bi, iwọ o ha ma mu u ṣe iranṣẹ lailai bi? 5 Iwọ ha le ba a ṣire bi ẹnipe ẹiyẹ ni, tabi iwọ o dè e fun awọn ọmọbinrin iranṣẹ rẹ? 6 Ẹgbẹ awọn apẹja yio ha ma tà a bi, nwọn o ha pin i lãrin awọn oniṣowo? 7 Iwọ le isọ awọ rẹ̀ kun fun irin abeti, tabi iwọ o sọ ori rẹ̀ kún fun ẹṣín apẹja. 8 Fi ọwọ rẹ le e lara, iwọ o ranti ìja na, iwọ kì yio ṣe bẹ̃ mọ. 9 Kiyesi i, abá nipasẹ rẹ̀ ni asan, ni kìki ìri rẹ̀ ara kì yio ha rọ̀ ọ wẹsi? 10 Kò si ẹni-alaiya lile ti o le iru u soke; njẹ tali o le duro niwaju rẹ̀? 11 Tani o ṣaju ṣe fun mi, ti emi iba fi san fun u? ohunkohun ti mbẹ labẹ ọrun gbogbo ti emi ni. 12 Emi kì yio fi ipin ara rẹ̀ pamọ, tabi ipá rẹ̀, tabi ihamọra rẹ̀ ti o li ẹwà. 13 Tani yio le iridi oju aṣọ apata rẹ̀, tabi tani o le isunmọ ọ̀na meji ehin rẹ̀. 14 Tani o le iṣi ilẹkun iwaju rẹ̀? ayika ehin rẹ̀ ni ìbẹru nla. 15 Ipẹ lile ni igberaga rẹ̀, o pade pọ mọtimọti bi ami edidi, 16 Ekini fi ara mọ ekeji tobẹ̃ ti afẹfẹ kò le iwọ̀ arin wọn. 17 Ekini fi ara mọra ekeji rẹ̀, nwọn lẹmọ pọ̀ ti a kò le iyà wọn. 18 Nipa sísin rẹ̀ imọlẹ a mọ́, oju rẹ̀ a si dabi ipénpeju owurọ. 19 Lati ẹnu rẹ̀ ni ọwọ́-iná ti ijade wá, ipẹpẹ iná a si ta jade. 20 Lati iho-imú rẹ̀ li ẽfin ti ijade wá, bi ẹnipe lati inu ikoko ti a fẹ́ iná ifefe labẹ rẹ̀. 21 Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade. 22 Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀. 23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò. 24 Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ. 25 Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu. 26 Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa. 27 O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù. 28 Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko. 29 O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ. 30 Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ. 31 O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra. 32 O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo. 33 Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru. 34 O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga.

Jobu 42

1 NIGBANA ni Jobu da OLUWA lohùn o si wipe, 2 Emi mọ̀ pe, iwọ le iṣe ohun gbogbo, ati pe, kò si iro-inu ti a le ifasẹhin kuro lọdọ rẹ. 3 Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye. 4 Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye. 5 Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ. 6 Njẹ nitorina emi korira ara mi, mo si ronupiwada ṣe tóto ninu ekuru ati ẽru.

Ìparí

7 Bẹ̃li o si ri, lẹhin igbati OLUWA ti sọ ọ̀rọ wọnyi tan fun Jobu, OLUWA si wi fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu si ọ ati si awọn ọrẹ́ rẹ mejeji, nitoripe ẹnyin kò sọ̀rọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ. 8 Nitorina ẹ mu akọ ẹgbọrọ malu meje, ati àgbo meje, ki ẹ si tọ̀ Jobu iranṣẹ mi lọ, ki ẹ si fi rú ẹbọ sisun fun ara nyin: Jobu iranṣẹ mi yio si gbadura fun nyin: nitoripe oju rẹ̀ ni mo gbà; ki emi ki o má ba ṣe si nyin bi iṣina nyin, niti ẹnyin kò sọ̀rọ ohun ti o tọ́ si mi bi Jobu iranṣẹ mi. 9 Bẹ̃ni Elifasi, ara Tema, ati Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama lọ, nwọn si ṣe gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: OLUWA si gbà oju Jobu. 10 OLUWA si yi igbekun Jobu pada, nigbati o gbadura fun awọn ọrẹ rẹ̀: OLUWA si busi ohun gbogbo ti Jobu ni rí ni iṣẹpo meji. 11 Nigbana ni gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn arabinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o ti ṣe ojulumọ rẹ̀ rí, nwọn mba a jẹun ninu ile rẹ̀, nwọn si ṣe idaro rẹ̀, nwọn si ṣipẹ fun nitori ibí gbogbo ti OLUWA ti mu ba a: olukuluku enia pẹlu si bùn u ni ike owo-kọkan ati olukuluku ni oruka wura eti kọ̃kan. 12 Bẹ̃li OLUWA bukún igbẹhin Jobu jù iṣaju rẹ̀ lọ; o si ni ẹgba-meje agutan, ẹgba-mẹta ibakasiẹ, ati ẹgbẹrun ajaga ọda-malu, ati ẹgbẹrun abo kẹtẹkẹtẹ. 13 O si ni ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. 14 O si sọ orukọ akọbi ni Jemima, ati orukọ ekeji ni Kesia, ati orukọ ẹkẹta ni Keren-happuki. 15 Ati ni gbogbo ilẹ na, a kò ri obinrin ti o li ẹwa bi ọmọbinrin Jobu; baba wọn si pinlẹ fun wọn ninu awọn arakunrin wọn. 16 Lẹhin eyi Jobu wà li aiye li ogoje ọdun, o si ri awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ani iran mẹrin. 17 Bẹ̃ni Jobu kú, o gbó, o si kún fun ọjọ.

Psalmu 1

Ayọ̀ Tòótọ́

IWE KINNI

1 IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn. 2 Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru. 3 Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede. 4 Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ. 5 Nitorina awọn enia buburu kì yio dide duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio le duro li awujọ awọn olododo. 6 Nitori Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe.

Psalmu 2

Àyànfẹ́ Ọlọrun

1 ẼṢE ti awọn orilẹ-ède fi nbinu fùfu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan? 2 Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe, 3 Ẹ jẹ ki a fa ìde wọn já, ki a si mu okùn wọn kuro li ọdọ wa. 4 Ẹniti o joko li ọrun yio rẹrin: Oluwa yio yọ ṣùti si wọn. 5 Nigbana ni yio sọ̀rọ si wọn ni ibinu rẹ̀, yio si yọ wọn lẹnu ninu ibinujẹ rẹ̀ kikan. 6 Ṣugbọn mo ti fi Ọba mi jẹ lori Sioni, òke mimọ́ mi. 7 Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ. 8 Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn orilẹ-ède fun ọ ni ini rẹ, ati iha opin ilẹ li ọrọ̀-ilẹ rẹ. 9 Ọpá irin ni iwọ o fi fọ́ wọn; iwọ o si rún wọn womuwomu, bi ohun èlo amọ̀. 10 Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n, ẹnyin ọba: ki a si kọ́ nyin, ẹnyin onidajọ aiye. 11 Ẹ fi ìbẹru sìn Oluwa, ẹ si ma yọ̀ ti ẹnyin ti iwarìri. 12 Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.

Psalmu 3

Adura Òwúrọ̀ fun Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, awọn ti nyọ mi li ẹnu ti npọ̀ to yi! ọ̀pọlọpọ li awọn ti o dide si mi. 2 Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun. 3 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke. 4 Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. 5 Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin, 6 Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka. 7 Dide Oluwa; gbà mi, Ọlọrun mi: nitori iwọ li o lù gbogbo awọn ọta mi li egungun ẹrẹkẹ; iwọ si ká ehin awọn enia buburu. 8 Ti Oluwa ni igbala: ibukún rẹ si mbẹ lara awọn enia rẹ.

Psalmu 4

Igbẹkẹle OLUWA

1 GBOHÙN mi nigbati mo ba npè, Ọlọrun ododo mi: iwọ li o da mi ni ìde ninu ipọnju; ṣe ojurere fun mi, ki o si gbọ́ adura mi. 2 Ẹnyin ọmọ enia, ẹ o ti sọ ogo mi di itiju pẹ to? ẹnyin o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wá eke iṣe? 3 Ṣugbọn ki ẹ mọ̀ pe Oluwa yà ẹni ayanfẹ sọ̀tọ fun ara rẹ̀: Oluwa yio gbọ́ nigbati mo ba kepè e. 4 Ẹ duro ninu ẹ̀ru, ẹ má si ṣe ṣẹ̀; ẹ ba ọkàn nyin sọ̀rọ lori ẹní nyin, ki ẹ si duro jẹ. 5 Ẹ ru ẹbọ ododo, ki ẹ si gbẹkẹ nyin le Oluwa. 6 Ẹni pupọ li o nwipe, Tani yio ṣe rere fun wa? Oluwa, iwọ gbé imọlẹ oju rẹ soke si wa lara. 7 Iwọ ti fi ayọ̀ si mi ni inu, jù igba na lọ ti ọkà wọn ati ọti-waini wọn di pupọ̀. 8 Emi o dubulẹ pẹlu li alafia, emi o si sùn; nitori iwọ, Oluwa, nikanṣoṣo li o nmu mi joko li ailewu.

Psalmu 5

Adura Ààbò

1 FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi. 2 Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si. 3 Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke. 4 Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe. 5 Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. 6 Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan. 7 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o wá sinu ile rẹ li ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ: ninu ẹ̀ru rẹ li emi o tẹriba si iha tempili mimọ́ rẹ. 8 Tọ́ mi, Oluwa, ninu ododo rẹ, nitori awọn ọta mi: mu ọ̀na rẹ tọ́ tàra niwaju mi. 9 Nitori ti otitọ kan kò si li ẹnu ẹnikẹni wọn; ikakika ni iha inu wọn; isa-okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi npọ́nni. 10 Iwọ da wọn lẹbi, Ọlọrun; ki nwọn ki o ti ipa ìmọ ara wọn ṣubu; já wọn kuro nitori ọ̀pọlọpọ irekọja wọn; nitori ti nwọn ti ṣọ̀tẹ si ọ. 11 Nigbana ni gbogbo awọn ti ngbẹkẹle ọ yio yọ̀; lai nwọn o ma ho fun ayọ̀, nitoriti iwọ dabobo wọn: ati awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu yio ma yọ̀ ninu rẹ. 12 Nitori iwọ, Oluwa, ni yio bukún fun olododo; oju-rere ni iwọ o fi yi i ka bi asà.

Psalmu 6

Adura nígbà ìyọnu

1 OLUWA, máṣe ba mi wi ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má ṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. 2 Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi. 3 Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to! 4 Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ. 5 Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ? 6 Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi. 7 Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi. 8 Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi. 9 Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi. 10 Oju yio tì gbogbo awọn ọta mi, ara yio sì kan wọn gogo: nwọn o pada, oju yio tì wọn lojíji.

Psalmu 7

Ọlọrun Onídàájọ́ Òdodo

1 OLUWA, Ọlọrun mi, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: gbà mi lọwọ gbogbo awọn ti nṣe inunibini si mi, ki o si yọ mi kuro. 2 Ki o má ba fa ọkàn mi ya bi kiniun, a yà a pẹrẹpẹrẹ, nigbati kò si oluranlọwọ. 3 Oluwa, Ọlọrun mi, bi mo ba ṣe eyi, bi ẹ̀ṣẹ ba mbẹ li ọwọ mi; 4 Bi mo ba fi ibi san a fun ẹniti temi tirẹ̀ wà li alafia; (nitõtọ ẹniti nṣe ọta mi li ainidi, emi tilẹ gbà a là:) 5 Jẹ ki ọta ki o ṣe inunibini si ọkàn mi, ki o si mu u; ki o tẹ̀ ẹmi mi mọlẹ, ki o si fi ọlá mi le inu ekuru. 6 Dide Oluwa, ni ibinu rẹ! gbé ara rẹ soke nitori ikannu awọn ọta mi: ki iwọ ki o si jí fun mi si idajọ ti iwọ ti pa li aṣẹ. 7 Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke. 8 Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi. 9 Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò. 10 Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya. 11 Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ: 12 Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ. 13 O si ti pèse elo ikú silẹ fun u; o ti ṣe awọn ọfa rẹ̀ ni oniná. 14 Kiyesi i, o nrọbi ẹ̀ṣẹ, o si loyun ìwa-ìka, o si bí eké jade. 15 O ti wà ọ̀fin, o gbẹ́ ẹ, o si bọ́ sinu iho ti on na wà. 16 Ìwa-ika rẹ̀ yio si pada si ori ara rẹ̀, ati ìwa-agbara rẹ̀ yio si sọ̀kalẹ bọ̀ si atari ara rẹ̀. 17 Emi o yìn Oluwa gẹgẹ bi ododo rẹ̀: emi o si kọrin iyìn si orukọ Oluwa Ọga-ogo julọ.

Psalmu 8

Ògo OLUWA ati ipò eniyan

1 OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun. 2 Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ. 3 Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ. 4 Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò. 5 Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade. 6 Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀; 7 Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ; 8 Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun. 9 Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye!

Psalmu 9

Ọpẹ́ fún Ọlọrun nítorí Ìdájọ́ Òdodo Rẹ̀

1 EMI o fi gbogbo aiya mi yìn Oluwa: emi o fi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ hàn. 2 Emi o yọ̀, emi o si ṣe inu-didùn ninu rẹ, emi o si kọrin iyìn si orukọ rẹ, iwọ Ọga-ogo julọ. 3 Nigbati awọn ọta mi ba pẹhinda, nwọn o ṣubu, nwọn o si ṣegbe ni iwaju rẹ. 4 Nitori iwọ li o ti mu idajọ mi ati idi ọ̀ran mi duro; iwọ li o joko lori itẹ́, ti o nṣe idajọ ododo. 5 Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai. 6 Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn. 7 Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ. 8 On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa. 9 Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju. 10 Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ. 11 Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. 12 Nigbati o wadi ẹjọ-ẹ̀jẹ, o ranti wọn: on kò si gbagbe ẹkún awọn olupọnju. 13 Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú. 14 Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ. 15 Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́. 16 A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u. 17 Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun. 18 Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai. 19 Oluwa, dide; máṣe jẹ ki enia ki o bori: jẹ ki a ṣe idajọ awọn orilẹ-ède niwaju rẹ. 20 Dẹru ba wọn, Oluwa: ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ ara wọn pe, enia ṣa ni nwọn.

Psalmu 10

Adura Olùpọ́njú

1 EṢE ti iwọ fi duro li òkere rere, Oluwa; ẽṣe ti iwọ fi fi ara pamọ́ ni igba ipọnju. 2 Ninu igberaga li enia buburu nṣe inunibini si awọn talaka: ninu arekereke ti nwọn rò ni ki a ti mu wọn. 3 Nitori enia buburu nṣogo ifẹ ọkàn rẹ̀, o si nsure fun olojukokoro, o si nkẹgan Oluwa. 4 Enia buburu, nipa igberaga oju rẹ̀, kò fẹ ṣe afẹri Ọlọrun: Ọlọrun kò si ni gbogbo ironu rẹ̀. 5 Ọ̀na rẹ̀ nlọ siwaju nigbagbogbo; idajọ rẹ jina rere kuro li oju rẹ̀; gbogbo awọn ọta rẹ̀ li o nfẹ̀ si. 6 O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, A kì yio ṣi mi ni ipò: lati irandiran emi kì yio si ninu ipọnju. 7 Ẹnu rẹ̀ kún fun egún, ati fun ẹ̀tan, ati fun itanjẹ: ìwa-ìka ati ìwa-asan mbẹ labẹ ahọn rẹ̀. 8 O joko ni buba ni ileto wọnni: ni ibi ìkọkọ wọnni li o npa awọn alaiṣẹ̀: oju rẹ̀ nṣọ́ awọn talaka nikọkọ. 9 O lùmọ ni ibi ìkọkọ bi kiniun ninu pantiri: o lùmọ lati mu talaka: a si mu talaka, nigbati o ba fà a sinu àwọn rẹ̀. 10 O ba, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ki talaka ki o le bọ́ si ọwọ agbara rẹ̀. 11 O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun ti gbagbe: o pa oju rẹ̀ mọ́; on kì yio ri i lailai. 12 Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju. 13 Ẽṣe ti enia buburu fi ngàn Ọlọrun? o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Iwọ kì yio bère. 14 Iwọ ti ri i; nitori iwọ nwò ìwa-ìka ati iwọsi, lati fi ọ̀ran na le ọwọ rẹ; talaka fi ara rẹ̀ le ọ lọwọ; iwọ li oluranlọwọ alaini-baba. 15 Ṣẹ́ apa enia buburu, ati ti ọkunrin ibi nì: iwọ wá ìwa-buburu rẹ̀ ri, titi iwọ kì yio fi ri i mọ́. 16 Oluwa li ọba lai ati lailai: awọn keferi run kuro ni ilẹ rẹ̀. 17 Oluwa, iwọ ti gbọ́ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i. 18 Lati ṣe idajọ alaini-baba ati ẹni-inilara, ki ọkunrin aiye ki o máṣe daiya-fo-ni mọ́.

Psalmu 11

OLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo

1 OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin? 2 Sa kiyesi i, awọn enia buburu ti fà ọrun wọn le, nwọn ti fi ọfa sùn li oju ọṣán, ki nwọn ki o le ta a li òkunkun si ọlọkàn diduro. 3 Bi ipilẹ ba bajẹ, kili olododo yio ṣe? 4 Oluwa mbẹ ninu tempili mimọ́ rẹ̀, itẹ́ Oluwa mbẹ li ọrun: oju rẹ̀ nwò, ipenpeju rẹ̀ ndán awọn ọmọ enia wò. 5 Oluwa ndán olododo wò: ṣugbọn enia buburu ati ẹniti nfẹ ìwa-agbara, ọkàn rẹ̀ korira. 6 Lori enia buburu ni yio rọjo, ẹyín gbigbona ati imi-ọjọ ati iji gbigbona: eyi ni ipin ago wọn. 7 Nitori olododo li Oluwa, o fẹ ododo; awọn ẹniti o duro-ṣinṣin yio ri oju rẹ̀.

Psalmu 12

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 GBÀ-NI Oluwa; nitori awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun dasẹ̀; nitori awọn olõtọ dasẹ̀ kuro ninu awọn ọmọ enia. 2 Olukuluku wọn mba ẹnikeji rẹ̀ sọ asan; ète ipọnni ati ọkàn meji ni nwọn fi nsọ. 3 Oluwa yio ké gbogbo ète ipọnni kuro, ati ahọn ti nsọ̀rọ ohun nla. 4 Ti o wipe, Ahọn wa li awa o fi ṣẹgun; ète wa ni ti wa: tani iṣe oluwa wa? 5 Nitori inira awọn talaka, nitori imi-ẹ̀dun awọn alaini, Oluwa wipe, nigbayi li emi o dide; emi o si yọ ọ si ibi ailewu kuro lọwọ ẹniti nfẹ̀ si i. 6 Ọ̀rọ Oluwa, ọ̀rọ funfun ni, bi fadaka ti a yọ́ ni ileru erupẹ, ti a dà ni igba meje. 7 Iwọ o pa wọn mọ́, Oluwa, iwọ o pa olukuluku wọn mọ́ kuro lọwọ iran yi lailai. 8 Awọn enia buburu nrìn ni iha gbogbo, nigbati a ba gbé awọn enia-kenia leke.

Psalmu 13

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 IWỌ o ti gbagbe mi pẹ to, Oluwa, lailai? iwọ o ti pa oju rẹ mọ́ pẹ to kuro lara mi? 2 Emi o ti ma gbìmọ li ọkàn mi pẹ to? ti emi o ma ni ibinujẹ li ọkàn mi lojojumọ? ọta mi yio ti gberaga sori mi pẹ to? 3 Rò o, ki o si gbohùn mi, Oluwa Ọlọrun mi: mu oju mi mọlẹ, ki emi ki o má ba sùn orun ikú. 4 Ki ọta mi ki o má ba wipe, emi ti ṣẹgun rẹ̀; awọn ti nyọ mi lẹnu a si ma yọ̀, nigbati a ba ṣi mi nipò. 5 Ṣugbọn emi o gbẹkẹle ãnu rẹ; ọkàn mi yio yọ̀ ni igbala rẹ. 6 Emi o ma kọrin si Oluwa, nitoriti o ṣe fun mi li ọ̀pọlọpọ.

Psalmu 14

Èrè Òmùgọ̀

1 AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ, nwọn si nṣe iṣẹ irira, kò si ẹniti nṣe rere. 2 Oluwa bojuwò lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun. 3 Gbogbo wọn li o si jumọ yà si apakan, nwọn si di elẽri patapata; kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan. 4 Gbogbo awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ kò ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun, nwọn kò si kepè Oluwa. 5 Nibẹ ni ẹ̀ru bà wọn gidigidi: nitoriti Ọlọrun mbẹ ninu iran olododo. 6 Ẹnyin dojutì ìmọ awọn talaka, ṣugbọn Oluwa li àbo rẹ̀. 7 Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá! nigbati Oluwa ba mu ikólọ awọn enia rẹ̀ pada bọ̀, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.

Psalmu 15

Ìwà tí Ọlọrun Fẹ́

1 OLUWA, tani yio ma ṣe atipo ninu agọ rẹ? tani yio ma gbe inu òke mimọ́ rẹ? 2 Ẹniti o nrìn dede, ti nṣiṣẹ ododo, ti o si nsọ otitọ inu rẹ̀. 3 Ẹniti kò fi ahọn rẹ̀ sọ̀rọ ẹni lẹhin, ti kò si ṣe ibi si ẹnikeji rẹ̀, ti kò si gbà ọ̀rọ ẹ̀gan si ẹnikeji rẹ̀. 4 Li oju ẹniti enia-kenia di gigàn; ṣugbọn a ma bu ọla fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa. Ẹniti o bura si ibi ara rẹ̀, ti kò si yipada. 5 Ẹniti kò fi owo rẹ̀ gbà èle, ti kò si gbà owo ẹ̀bẹ si alaiṣẹ. Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi kì yio yẹsẹ lailai.

Psalmu 16

Mo Sá di OLUWA

1 ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le. 2 Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ. 3 Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà. 4 Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi. 5 Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. 6 Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere. 7 Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru. 8 Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò. 9 Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti. 10 Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹ̃ni iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ. 11 Iwọ o fi ipa ọ̀na ìye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ̀ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai.

Psalmu 17

Adura fún Ìdáláre

1 GBỌ́ otiọ́, Oluwa, fiyesi igbe mi, fi eti si adura mi, ti kò ti ète ẹ̀tan jade. 2 Jẹ ki idajọ mi ki o ma ti iwaju rẹ jade wá: jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ohun ti o ṣe dẽde. 3 Iwọ ti dan aiya mi wò; iwọ ti bẹ̀ ẹ wò li oru; iwọ ti wadi mi, iwọ kò ri nkan; emi ti pinnu rẹ̀ pe, ẹnu mi kì yio ṣẹ̀. 4 Niti iṣẹ enia, nipa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ emi ti pa ara mi mọ́ kuro ni ipa alaparun. 5 Fi ìrin mi le ilẹ ni ipa rẹ, ki atẹlẹ ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. 6 Emi ti nkepè ọ, nitori pe iwọ o gbohùn mi, Ọlọrun: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbọ́ ọ̀rọ mi: 7 Fi iṣeun ifẹ iyanu rẹ hàn, iwọ ti o fi ọwọ ọtún rẹ gbà awọn ti o gbẹkẹle ọ là, lọwọ awọn ti o dide si wọn. 8 Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ, 9 Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri. 10 Nwọn fi ọ̀ra sé aiya wọn, ẹnu wọn ni nwọn fi nsọ̀rọ igberaga. 11 Nwọn ti yi wa ká nisisiyi ninu ìrin wa; nwọn ti gbé oju wọn le ati wọ́ wa silẹ: 12 Bi kiniun ti nṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ̀, ati bi ọmọ kiniun ti o mba ni ibi ìkọkọ. 13 Dide, Oluwa, ṣaju rẹ̀, rẹ̀ ẹ silẹ: gbà ọkàn mi lọwọ awọn enia buburu, ti iṣe idà rẹ: 14 Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn. 15 Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.

Psalmu 18

Orin Ìṣẹ́gun

1 EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi. 2 Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. 3 Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. 4 Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi. 5 Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu. 6 Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀. 7 Nigbana ni ilẹ mì, o si wariri: ipilẹ òke pẹlu ṣidi, o si mì, nitoriti o binu. 8 Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀. 9 O tẹri ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ wá: òkunkun si mbẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. 10 O si gùn ori kerubu o si fò: nitõtọ, o nra lori iyẹ-apa afẹ́fẹ́. 11 O fi òkunkun ṣe ibi ìkọkọ rẹ̀: ani agọ́ rẹ̀ yi i ka kiri; omi dudu, ati awọsanma oju-ọrun ṣiṣu dudu. 12 Nipa imọlẹ iwaju rẹ̀, awọsanma ṣiṣu dùdu rẹ̀ kọja lọ, yinyín ati ẹyín iná. 13 Oluwa sán ãra pẹlu li ọrun, Ọga-ogo si fọ̀ ohùn rẹ̀: yinyín ati ẹyín iná! 14 Lõtọ, o rán ọfa rẹ̀ jade, o si tú wọn ká: ọ̀pọlọpọ manamana li o si fi ṣẹ́ wọn tũtu. 15 Nigbana li awowò omi odò hàn, a si ri ipilẹ aiye nipa ibawi rẹ, Oluwa, nipa fifun ẽmi iho imu rẹ. 16 O ranṣẹ́ lati òke wá, o mu mi, o fà mi jade wá lati inu omi nla. 17 O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, ati lọwọ awọn ti o korira mi; nitori nwọn li agbara jù mi lọ. 18 Nwọn dojukọ mi li ọjọ ipọnju mi: ṣugbọn Oluwa li alafẹhintì mi. 19 O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi. 20 Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi. 21 Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi. 22 Nitori pe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi, bẹ̃li emi kò si yẹ̀ ofin rẹ̀ kuro lọdọ mi. 23 Emi si duro ṣinṣin pẹlu rẹ̀, emi si paramọ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi. 24 Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀. 25 Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu; fun ẹniti o duro-ṣinṣin ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni diduro-ṣinṣin. 26 Fun ọlọkàn-mimọ́ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni ọlọkàn-mimọ́; ati fun ọlọkàn-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn li onroro. 27 Nitori iwọ o gbà awọn olupọnju; ṣugbọn iwọ o sọ oju igberaga kalẹ. 28 Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi. 29 Nitori pe pẹlu rẹ emi sure là inu ogun lọ: ati pẹlu Ọlọrun mi emi fò odi kan. 30 Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. 31 Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa? 32 Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé. 33 O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi. 34 O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. 35 Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. 36 Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. 37 Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn. 38 Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi. 39 Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi. 40 Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run. 41 Nwọn kigbe, ṣugbọn kò si ẹniti o gbà wọn; ani si Oluwa, ṣugbọn kò dá wọn li ohùn. 42 Nigbana ni mo gún wọn kunna bi ekuru niwaju afẹfẹ: mo kó wọn jade bi ohun ẹ̀gbin ni ita. 43 Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi. 44 Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi. 45 Aiya yio pá awọn alejo, nwọn o si fi ibẹ̀ru jade ni ibi kọlọfin wọn. 46 Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke. 47 Ọlọrun li o ngbẹsan mi, ti o si nṣẹ́ awọn enia fun mi. 48 O gbà mi lọwọ awọn ọta mi: pẹlupẹlu iwọ gbé mi leke jù awọn ti o dide si mi lọ; iwọ ti gbà mi lọwọ ọkunrin alagbara nì. 49 Nitorina li emi ṣe fi iyìn fun ọ, Oluwa, li awujọ awọn orilẹ-ède, emi o si ma kọrin iyìn si orukọ rẹ. 50 Ẹniti o fi igbala nla fun Ọba rẹ̀; o si fi ãnu hàn fun Ẹni-ororo rẹ̀, fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ lailai.

Psalmu 19

Ògo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá

1 AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han. 2 Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn. 3 Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn. 4 Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun. 5 Ti o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rẹ̀ wá, ti o si yọ̀ bi ọkunrin alagbara lati sure ije. 6 Ijadelọ rẹ̀ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rẹ̀ si de ipinlẹ rẹ̀: kò si si ohun ti o fi ara pamọ́ kuro ninu õru rẹ̀.

Òfin OLUWA

7 Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n. 8 Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju. 9 Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn. 10 Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin. 11 Pẹlupẹlu nipa wọn li a ti ṣi iranṣẹ rẹ leti; ati ni pipamọ́ wọn ere pipọ̀ mbẹ. 12 Tali o le mọ̀ iṣina rẹ̀? wẹ̀ mi mọ́ kuro ninu iṣiṣe ìkọkọ mi. 13 Fà iranṣẹ rẹ sẹhin pẹlu kuro ninu ẹ̀ṣẹ ikugbu: máṣe jẹ ki nwọn ki o jọba lori mi: nigbana li emi o duro ṣinṣin, emi o si ṣe alaijẹbi kuro ninu ẹ̀ṣẹ nla nì. 14 Jẹ ki ọ̀rọ ẹnu mi, ati iṣaro ọkàn mi, ki o ṣe itẹwọgba li oju rẹ, Oluwa, agbara mi, ati oludande mi.

Psalmu 20

Adura Ìṣẹ́gun

1 KI Oluwa ki o gbohùn rẹ li ọjọ ipọnju; orukọ Ọlọrun Jakobu ki o dàbobo ọ. 2 Ki o rán iranlọwọ si ọ lati ibi-mimọ́ wá, ki o si tì ọ lẹhin lati Sioni wá. 3 Ki o ranti ẹbọ-ọrẹ rẹ gbogbo, ki o si gbà ẹbọ sisun rẹ. 4 Ki o fi fun ọ gẹgẹ bi ti inu rẹ, ki o si mu gbogbo ìmọ rẹ ṣẹ. 5 Awa o ma kọrin ayọ̀ igbala rẹ, ati li orukọ Ọlọrun wa li awa o fi ọpágun wa de ilẹ; ki Oluwa ki o mu gbogbo ibère rẹ ṣẹ. 6 Nigbayi ni mo to mọ̀ pe Oluwa gbà Ẹni-ororo rẹ̀ là; yio gbọ́ ọ lati ọrun mimọ́ rẹ̀ wá nipa agbara igbala ọwọ ọ̀tun rẹ̀. 7 Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹkẹ́, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ Oluwa Ọlọrun wa. 8 Nwọn wolẹ, nwọn si ṣubu: ṣugbọn awa dide awa si duro ṣinṣin. 9 Gbani, Oluwa, ki Ọba ki o gbọ nigbati awa ba nkigbe pe e.

Psalmu 21

Orin Ìṣẹ́gun

1 ỌBA yio ma yọ̀ li agbara rẹ, Oluwa; ati ni igbala rẹ, yio ti yọ̀ pọ̀ to! 2 Iwọ ti fi ifẹ ọkàn rẹ̀ fun u, iwọ kò si dù u ni ibère ẹnu rẹ̀. 3 Nitori iwọ ti fi ibukún ore kò o li ọ̀na, iwọ fi ade kiki wura de e li ori. 4 O tọrọ ẹmi lọwọ rẹ, iwọ si fi fun u, ani ọjọ gigùn lai ati lailai. 5 Ogo rẹ̀ pọ̀ ni igbala rẹ: iyìn ati ọlánla ni iwọ fi si i lara. 6 Nitori iwọ ti ṣe e li ẹni-ibukún fun jùlọ titi aiye: iwọ si fi oju rẹ mu u yọ̀ gidigidi. 7 Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada. 8 Ọwọ rẹ yio wá gbogbo awọn ọta rẹ ri: ọwọ ọtún rẹ ni yio wá awọn ti o korira rẹ ri. 9 Iwọ o ṣe wọn bi ileru onina ni igba ibinu rẹ: Oluwa yio gbé wọn mì ni ibinu rẹ̀, iná na yio si jó wọn pa. 10 Eso wọn ni iwọ o run kuro ni ilẹ, ati irú-ọmọ wọn kuro ninu awọn ọmọ enia. 11 Nitori ti nwọn nrò ibi si ọ: nwọn ngbìro ete ìwa-ibi, ti nwọn kì yio le ṣe. 12 Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn. 13 Ki iwọ ki ó ma leke, Oluwa, li agbara rẹ; bẹ̃li awa o ma kọrin, ti awa o si ma yìn agbara rẹ.

Psalmu 22

Igbe Ìrora ati Orin Ìyìn

1 ỌLỌRUN mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? ti iwọ si jina si igbala mi, ati si ohùn igbe mi? 2 Ọlọrun mi, emi nkigbe li ọsan, ṣugbọn iwọ kò dahùn: ati ni igba oru emi kò dakẹ. 3 Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do. 4 Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn. 5 Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu. 6 Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia. 7 Gbogbo awọn ti o ri mi nfi mi rẹrin ẹlẹya: nwọn nyọ ṣuti ète wọn, nwọn nmì ori pe, 8 Jẹ́ ki o gbẹkẹle Oluwa, on o gbà a là; jẹ ki o gbà a là nitori inu rẹ̀ dùn si i. 9 Ṣugbọn iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu wá: iwọ li o mu mi wà li ailewu, nigbati mo rọ̀ mọ́ ọmu iya mi. 10 Iwọ li a ti fi mi le lọwọ lati inu iya mi wá: iwọ li Ọlọrun mi lati inu iya mi wá. 11 Máṣe jina si mi; nitori ti iyọnu sunmọ etile; nitoriti kò si oluranlọwọ. 12 Akọ-malu pipọ̀ li o yi mi ka: malu Baṣani ti o lagbara rọ̀gba yi mi ka. 13 Nwọn yà ẹnu wọn si mi, bi kiniun ti ndọdẹ kiri, ti nké ramuramu. 14 A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi. 15 Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú. 16 Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ. 17 Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn. 18 Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi. 19 Ṣugbọn iwọ máṣe jina si mi, Oluwa: agbara mi, yara lati ràn mi lọwọ. 20 Gbà ọkàn mi lọwọ idà; ẹni mi kanna lọwọ agbara aja nì. 21 Gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì; ki iwọ ki o si gbohùn mi lati ibi iwo awọn agbanrere. 22 Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ, 23 Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli. 24 Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́. 25 Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. 26 Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai: 27 Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀. 28 Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède. 29 Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye. 30 Iru kan yio ma sìn i; a o si kà a ni iran kan fun Oluwa. 31 Nwọn o wá, nwọn o si ma sọ̀rọ ododo rẹ̀ fun awọn enia kan ti a o bí, pe, on li o ṣe eyi.

Psalmu 23

OLUWA ni Olùṣọ́-agutan mi

1 OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini. 2 O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́. 3 O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀. 4 Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu. 5 Iwọ tẹ́ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ. 6 Nitotọ, ire ati ãnu ni yio ma tọ̀ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai.

Psalmu 24

Ọba Atóbijù

1 TI Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀; aiye, ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ̀. 2 Nitoriti o fi idi rẹ̀ sọlẹ lori okun, o si gbé e kalẹ lori awọn iṣan-omi. 3 Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀? 4 Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan. 5 On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀. 6 Eyi ni iran awọn ti nṣe afẹri rẹ̀, ti nṣe afẹri rẹ, Ọlọrun Jakobu. 7 Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. 8 Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun. 9 Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. 10 Tali Ọba ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun; on na li Ọba ogo.

Psalmu 25

Adura fún ìtọ́sọ́nà ati Ààbò

1 OLUWA, iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. 2 Ọlọrun mi, emi gbẹkẹle ọ: máṣe jẹ ki oju ki o ti mi, máṣe jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ̀ mi. 3 Lõtọ, maṣe jẹ ki oju ki o tì ẹnikẹni ti o duro tì ọ: awọn ti nṣẹ̀ li ainidi ni oju yio tì. 4 Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ. 5 Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo. 6 Oluwa, ranti ãnu ati iṣeun-ifẹ rẹ ti o ni irọnu; nitoriti nwọn ti wà ni igba atijọ. 7 Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ igba-ewe mi, ati irekọja mi: gẹgẹ bi ãnu rẹ iwọ ranti mi, Oluwa, nitori ore rẹ: 8 Rere ati diduro-ṣinṣin ni Oluwa: nitorina ni yio ṣe ma kọ́ ẹlẹṣẹ li ọ̀na na. 9 Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀. 10 Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́. 11 Nitori orukọ rẹ, Oluwa, dari ẹ̀ṣẹ mi jì, nitori ti o tobi. 12 Ọkunrin wo li o bẹ̀ru Oluwa? on ni yio kọ́ li ọ̀na ti yio yàn. 13 Ọkàn rẹ̀ yio joko ninu ire, irú-ọmọ rẹ̀ yio si jogun aiye. 14 Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀. 15 Oju mi gbé soke si Oluwa lai; nitori ti yio fà ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọn na. 16 Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. 17 Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi. 18 Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi. 19 Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka. 20 Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ. 21 Jẹ ki ìwa-titọ ati iduro-ṣinṣin ki o pa mi mọ́: nitoriti mo duro tì ọ. 22 Rà Israeli pada, Ọlọrun, kuro ninu ìṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.

Psalmu 26

Adura Ẹni Rere

1 ṢE idajọ mi, Oluwa; nitori ti mo ti nrìn ninu ìwa titọ mi; emi ti gbẹkẹle Oluwa pẹlu; njẹ ẹsẹ mi kì yio yẹ̀. 2 Wadi mi, Oluwa, ki o si ridi mi; dán inu mi ati ọkàn mi wò. 3 Nitoriti iṣeun-ifẹ rẹ mbẹ niwaju mi: emi si ti nrìn ninu otitọ rẹ. 4 Emi kò ba ẹni asan joko, bẹ̃li emi kì yio ba awọn alayidayida wọle. 5 Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko. 6 Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa. 7 Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ. 8 Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ. 9 Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, tabi ẹmi mi pẹlu awọn enia-ẹ̀jẹ. 10 Li ọwọ ẹniti ìwa-ìka mbẹ, ọwọ ọtún wọn si kún fun abẹtẹlẹ. 11 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o ma rìn ninu ìwatitọ mi: rà mi pada, ki o si ṣãnu fun mi. 12 Ẹsẹ mi duro ni ibi titẹju: ninu awọn ijọ li emi o ma fi ibukún fun Oluwa.

Psalmu 27

Adura Ìyìn

1 OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi? 2 Nigbati awọn enia buburu, ani awọn ọta mi ati awọn abinuku mi sunmọ mi lati jẹ ẹran ara mi, nwọn kọsẹ, nwọn si ṣubu. 3 Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le. 4 Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀. 5 Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata. 6 Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa. 7 Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn. 8 Nigbati o wipe, Ẹ ma wa oju mi; ọkàn mi wi fun ọ pe, Oju rẹ, Oluwa, li emi o ma wá. 9 Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi; máṣe fi ibinu ṣa iranṣẹ rẹ tì: iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi; má fi mi silẹ, bẹ̃ni ki o máṣe kọ̀ mi, Ọlọrun igbala mi. 10 Nigbati baba ati iya mi kọ̀ mi silẹ, nigbana ni Oluwa yio tẹwọgbà mi. 11 Kọ́ mi li ọ̀na rẹ, Oluwa, ki o si tọ́ mi li ọ̀na titọ, nitori awọn ọta mi. 12 Máṣe fi mi le ifẹ awọn ọta mi lọwọ; nitori awọn ẹlẹri eke dide si mi, ati iru awọn ti nmí imí-ìkà. 13 Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alãye. 14 Duro de Oluwa; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de Oluwa.

Psalmu 28

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 IWỌ, Oluwa, apata mi li emi o kigbe pè, máṣe dakẹ si mi; bi iwọ ba dakẹ si mi, emi o dabi awọn ti o lọ sinu ihò. 2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi, nigbati mo ba nkigbe pè ọ, nigbati mo ba gbé ọwọ mi soke siha ibi-mimọ́ jùlọ rẹ. 3 Máṣe fà mi lọ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ti nsọ̀rọ alafia si aladugbo wọn, ṣugbọn ìwa-ìka mbẹ̀ li ọkàn wọn. 4 Fi fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, ati gẹgẹ bi ìwa buburu ete wọn, fi fun wọn nipa iṣẹ ọwọ wọn, fi ère wọn fun wọn. 5 Nitori ti nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, tabi iṣẹ ọwọ rẹ̀; on o run wọn, kì yio si gbé wọn ró. 6 Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi. 7 Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i. 8 Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀. 9 Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.

Psalmu 29

Agbára OLUWA ninu ìjì

1 Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa. 2 Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. 3 Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀. 4 Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla. 5 Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya. 6 O mu wọn fò pẹlu bi ọmọ-malu; Lebanoni on Sirioni bi ọmọ agbanrere. 7 Ohùn Oluwa nyà ọwọ iná, 8 Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi. 9 Ohùn Oluwa li o nmu abo agbọnrin bi, o si fi igbo didi hàn: ati ninu tempili rẹ̀ li olukuluku nsọ̀rọ ogo rẹ̀. 10 Oluwa joko lori iṣan-omi; nitõtọ, Oluwa joko bi Ọba lailai. 11 Oluwa yio fi agbara fun awọn enia rẹ̀; Oluwa yio fi alafia busi i fun awọn enia rẹ̀.

Psalmu 30

Adura Ọpẹ́

1 EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi. 2 Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da. 3 Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho. 4 Kọrin si Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́, ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀. 5 Nitoripe, ni iṣẹju kan ni ibinu rẹ̀ ipẹ́, li ojurere rẹ̀ ni ìye gbe wà; bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ̀ mbọ li owurọ. 6 Ati ninu alafia mi, emi ni, ipò mi kì yio pada lailai. 7 Oluwa, nipa oju-rere rẹ, iwọ ti mu òke mi duro ṣinṣin: nigbati iwọ pa oju rẹ mọ́, ẹnu yọ mi. 8 Emi kigbe pè ọ, Oluwa; ati si Oluwa li emi mbẹ̀bẹ gidigidi. 9 Ere kili o wà li ẹ̀jẹ mi, nigbati mo ba lọ sinu ihò? erupẹ ni yio ma yìn ọ bi? on ni yio ma sọ̀rọ otitọ rẹ bi? 10 Gbọ́, Oluwa, ki o si ṣãnu fun mi: Oluwa, iwọ ma ṣe oluranlọwọ mi. 11 Iwọ ti sọ ikãnu mi di ijó fun mi; iwọ ti bọ aṣọ-ọ̀fọ mi kuro, iwọ si fi ayọ̀ dì mi li àmure. 12 Nitori idi eyi ni ki ogo mi ki o le ma kọrin si ọ, ki o má si ṣe dakẹ. Oluwa Ọlọrun mi, emi o ma fi iyìn fun ọ lailai.

Psalmu 31

Adura Igbẹkẹ le Ọlọrun

1 OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ. 2 Dẹ eti rẹ silẹ si mi: gbà mi nisisiyi: iwọ ma ṣe apata agbara mi, ile-ãbò lati gba mi si. 3 Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi. 4 Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi. 5 Li ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le: iwọ li o ti rà mi pada, Oluwa Ọlọrun otitọ. 6 Emi ti korira awọn ẹniti nfiyesi eke asan: ṣugbọn emi gbẹkẹle Oluwa. 7 Emi o yọ̀, inu mi yio si dùn ninu ãnu rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti iṣẹ́ mi; iwọ ti mọ̀ ọkàn mi ninu ipọnju; 8 Iwọ kò si sé mi mọ́ si ọwọ ọta nì: iwọ fi ẹsẹ mi tẹlẹ ni ibi àye nla. 9 Ṣãnu fun mi, Oluwa, nitori ti emi wà ninu iṣẹ́: oju mi fi ibinujẹ run, ọkàn mi ati inu mi. 10 Emi fi ibinujẹ lò ọjọ mi, ati ọdun mi ti on ti imi-ẹ̀dun: agbara mi kú nitori ẹ̀ṣẹ mi, awọn egungun mi si run. 11 Emi di ẹni-ẹ̀gan lãrin awọn ọta mi gbogbo, pẹlupẹlu lãrin awọn aladugbo mi, mo si di ẹ̀ru fun awọn ojulumọ mi: awọn ti o ri mi lode nyẹra fun mi. 12 Emi ti di ẹni-igbagbe kuro ni ìye bi okú: emi dabi ohun-elo fifọ́. 13 Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro. 14 Ṣugbọn emi gbẹkẹle ọ, Oluwa: emi ni, Iwọ li Ọlọrun mi. 15 Igba mi mbẹ li ọwọ rẹ: gbà mi li ọwọ awọn ọta mi, ati li ọwọ awọn ti nṣe inunibini si mi, 16 Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara: gbà mi nitori ãnu rẹ. 17 Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú. 18 Awọn ète eke ni ki a mu dakẹ; ti nsọ̀rọ ohun buburu ni igberaga ati li ẹ̀gan si awọn olododo. 19 Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia! 20 Iwọ o pa wọn mọ́ ni ibi ìkọkọ iwaju rẹ kuro ninu idimọlu awọn enia; iwọ o pa wọn mọ́ ni ìkọkọ ninu agọ kan kuro ninu ija ahọn. 21 Olubukún ni Oluwa; nitori ti o ti fi iṣeun-ifẹ iyanu rẹ̀ hàn mi ni ilu olodi. 22 Nitori ti mo ti wi ni ikanju mi pe, A ke mi kuro niwaju rẹ: ṣugbọn iwọ gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi nigbati mo kepè ọ. 23 Ẹ fẹ Oluwa, gbogbo ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: Oluwa npa onigbagbọ́ mọ́, o si san a li ọ̀pọlọpọ fun ẹniti nṣe igberaga. 24 Ẹ tujuka, yio si mu nyin li aiya le, gbogbo ẹnyin ti o ni ireti niti Oluwa.

Psalmu 32

Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀

1 IBUKÚN ni fun awọn ti a dari irekọja wọn jì, ti a bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. 2 Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹ̀tan kò si. 3 Nigbati mo dakẹ, egungun mi di gbigbo nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ. 4 Nitori li ọsan ati li oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara: omi ara mi si dabi ọdá-ẹ̀run. 5 Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ mi li emi kò si fi pamọ́. Emi wipe, emi o jẹwọ ìrekọja mi fun Oluwa: iwọ si dari ẹbi ẹ̀ṣẹ mi jì. 6 Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀. 7 Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri. 8 Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ. 9 Ki ẹnyin ki o máṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti kò ni iyè ninu: ẹnu ẹniti a kò le ṣe aifi ijanu bọ̀, ki nwọn ki o má ba sunmọ ọ. 10 Ọ̀pọ ikãnu ni yio wà fun enia buburu: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹle Oluwa, ãnu ni yio yi i ka kiri. 11 Ki inu nyin ki o dùn niti Oluwa, ẹ si ma yọ̀, ẹnyin olododo; ẹ si ma kọrin fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti aiya nyin duro ṣinṣin.

Psalmu 33

Orin Ìyìn

1 ẸMA yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo: nitoriti iyìn yẹ fun ẹni-diduro-ṣinṣin. 2 Ẹ ma fi duru yìn Oluwa: ẹ ma fi ohun-elo olokùn mẹwa kọrin si i. 3 Ẹ kọ orin titun si i: ẹ ma fi ọgbọngbọn lù ohun ọnà orin pẹlu ariwo. 4 Nitori ti ọ̀rọ Oluwa tọ́: ati gbogbo iṣẹ rẹ̀ li a nṣe ninu otitọ. 5 O fẹ otitọ ati idajọ: ilẹ aiye kún fun ãnu Oluwa. 6 Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀. 7 O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura. 8 Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀. 9 Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin. 10 Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki. 11 Imọ Oluwa duro lailai, ìro inu rẹ̀ lati irandiran. 12 Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀. 13 Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia. 14 Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye. 15 O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn. 16 Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ. 17 Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ. 18 Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀; 19 Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan. 20 Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa. 21 Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́. 22 Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.

Psalmu 34

Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀

1 EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai. 2 Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn. 3 Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke. 4 Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi. 5 Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn. 6 Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: 7 Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn. 8 Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e. 9 Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, 10 Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara. 11 Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa. 12 Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere? 13 Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ. 14 Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀. 15 Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn. 16 Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ. 17 Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo. 18 Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là. 19 Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo. 20 O pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kò si ọkan ti o ṣẹ́ ninu wọn. 21 Ibi ni yio pa enia buburu; ati awọn ti o korira olododo yio jẹbi. 22 Oluwa rà ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e kì yio jẹbi.

Psalmu 35

Adura ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà. 2 Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi. 3 Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ. 4 Ki nwọn ki o dãmu, ki a si tì awọn ti nwá ọkàn mi loju: ki a si mu wọn pada, ki a si dãmu awọn ti ngbiro ipalara mi. 5 Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn. 6 Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn. 7 Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi. 8 Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si. 9 Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀. 10 Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun? 11 Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀. 12 Nwọn fi buburu san ore fun mi, lati sọ ọkàn mi di ofo. 13 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, nigbati ara wọn kò dá, aṣọ àwẹ li aṣọ mi: mo fi àwẹ rẹ̀ ọkàn mi silẹ; adura mi si pada si mi li aiya. 14 Emi ṣe ara mi bi ẹnipe ọrẹ tabi arakunrin mi tilẹ ni: emi fi ibinujẹ tẹriba, bi ẹniti nṣọ̀fọ iya rẹ̀. 15 Ṣugbọn ninu ipọnju mi nwọn yọ̀, nwọn si kó ara wọn jọ: awọn enia-kenia kó ara wọn jọ si mi, emi kò si mọ̀; nwọn fa mi ya, nwọn kò si dakẹ. 16 Pẹlu awọn àgabagebe ti iṣe ẹlẹya li apejẹ, nwọn npa ehin wọn si mi. 17 Oluwa iwọ o ti ma wò pẹ to? yọ ọkàn mi kuro ninu iparun wọn, ẹni mi kanna lọwọ awọn kiniun. 18 Emi o ṣọpẹ fun ọ ninu ajọ nla: emi o ma yìn ọ li awujọ ọ̀pọ enia. 19 Máṣe jẹ ki awọn ti nṣe ọta mi lodi ki o yọ̀ mi; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki awọn ti o korira mi li ainidi ki o ma ṣẹju si mi. 20 Nitori ti nwọn kò sọ̀rọ alafia: ṣugbọn nwọn humọ ọ̀ran ẹ̀tan si awọn enia jẹjẹ ilẹ na. 21 Nitotọ, nwọn ya ẹnu wọn silẹ si mi, nwọn wipe, A! ã! oju wa ti ri i! 22 Eyi ni iwọ ti ri, Oluwa: máṣe dakẹ: Oluwa máṣe jina si mi. 23 Rú ara rẹ soke, ki o si ji si idajọ mi, ati si ọ̀ran mi, Ọlọrun mi ati Oluwa mi. 24 Ṣe idajọ mi, Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi ododo rẹ, ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o yọ̀ mi. 25 Máṣe jẹ ki nwọn kí o wi ninu ọkàn wọn pe, A! bẹ̃li awa nfẹ ẹ: máṣe jẹ ki nwọn ki o wipe, Awa ti gbé e mì. 26 Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si dãmu pọ̀, ti nyọ̀ si ifarapa mi: ki a fi itiju ati àbuku wọ̀ wọn ni aṣọ, ti ngberaga si mi. 27 Jẹ ki nwọn ki o ma hó fun ayọ̀, ki nwọn ki o si ma ṣe inu-didùn, ti nṣe oju-rere si ododo mi: lõtọ ki nwọn ki o ma wi titi pe, Oluwa ni ki a ma gbega, ti o ni inu-didùn si alafia iranṣẹ rẹ̀. 28 Ahọn mi yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ, ati ti iyìn rẹ ni gbogbo ọjọ.

Psalmu 36

Ìwà ìkà

1 IREKỌJA enia buburu wi ninu ọkàn mi pe; ẹ̀ru Ọlọrun kò si niwaju rẹ̀. 2 Nitoriti o npọ́n ara rẹ̀ li oju ara rẹ̀, titi a o fi ri ẹ̀ṣẹ rẹ̀ lati korira; 3 Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ li ẹ̀ṣẹ on ẹ̀tan: o ti fi ọgbọ́n ati iṣe rere silẹ, 4 O ngbèro ìwa-ika lori ẹni rẹ̀: o gba ọ̀na ti kò dara; on kò korira ibi.

Oore Ọlọrun

5 Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma. 6 Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́. 7 Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ. 8 Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ. 9 Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ. 10 Mu iṣeun ifẹ rẹ pẹ si awọn ti o mọ̀ ọ; ati ododo rẹ fun awọn alaiyà diduro. 11 Máṣe jẹ ki ẹsẹ agberaga ki o wá si mi, ki o má si jẹ ki ọwọ enia buburu ki o ṣi mi ni ipò. 12 Nibẹ li awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ gbe ṣubu: a rẹ̀ wọn silẹ, nwọn kì yio si le dide.

Psalmu 37

Ìgbẹ̀yìn Àwọn Eniyan Burúkú

1 MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. 2 Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù. 3 Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ. 4 Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ. 5 Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ. 6 Yio si mu ododo rẹ jade bi imọlẹ, ati idajọ rẹ bi ọsángangan. 7 Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ. 8 Dakẹ inu-bibi, ki o si kọ̀ ikannu silẹ: máṣe ikanra, ki o má ba ṣe buburu pẹlu. 9 Nitori ti a o ke awọn oluṣe-buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yio jogun aiye. 10 Nitori pe nigba diẹ, awọn enia buburu kì yio si: nitotọ iwọ o fi ara balẹ wò ipò rẹ̀, kì yio si si. 11 Ṣugbọn awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didùn ninu ọ̀pọlọpọ alafia. 12 Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara. 13 Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀. 14 Awọn enia buburu ti fà idà yọ, nwọn si ti fà ọrun wọn le, lati sọ talaka ati alaini kalẹ, ati lati pa iru awọn ti nrin li ọ̀na titọ. 15 Idà wọn yio wọ̀ aiya wọn lọ, ọrun wọn yio si ṣẹ́. 16 Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ̀ ọ̀pọ enia buburu. 17 Nitoriti a o ṣẹ́ apa awọn enia buburu: ṣugbọn Oluwa di olododo mu. 18 Oluwa mọ̀ ọjọ ẹni iduro-ṣinṣin: ati ilẹ-ini wọn yio wà lailai. 19 Oju kì yio tì wọn ni igba ibi: ati li ọjọ ìyan a o tẹ́ wọn lọrun. 20 Ṣugbọn awọn enia buburu yio ṣegbe, awọn ọta Oluwa yio dabi ẹwà oko-tutu: nwọn o run; ẹ̃fin ni nwọn o run si. 21 Awọn enia buburu wín, nwọn kò si pada san: ṣugbọn olododo a ma ṣãnu, a si ma fi funni. 22 Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro. 23 A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀. 24 Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu. 25 Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ. 26 Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀. 27 Kuro ninu ibi ki o si ma ṣe rere; ki o si ma joko lailai. 28 Nitoriti Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ̀ awọn enia mimọ́ rẹ̀ silẹ; a si pa wọn mọ́ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro. 29 Olododo ni yio jogun aiye, yio si ma gbe inu rẹ̀ lailai. 30 Ẹnu olododo ni ima sọ̀rọ ọgbọ́n, ahọn rẹ̀ a si ma sọ̀rọ idajọ. 31 Ofin Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li aiya rẹ̀; ọkan ninu ìrin rẹ̀ kì yio yẹ̀. 32 Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a. 33 Oluwa kì yio fi i le e lọwọ, kì yio si da a lẹbi, nigbati a ba nṣe idajọ rẹ̀. 34 Duro de Oluwa, ki o si ma pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, yio si gbé ọ leke lati jogun aiye: nigbati a ba ké awọn enia buburu kuro, iwọ o ri i. 35 Emi ti nri enia buburu, ẹni ìwa-ika, o si fi ara rẹ̀ gbilẹ bi igi tutu nla. 36 Ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò sí mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i. 37 Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na. 38 Ṣugbọn awọn alarekọja li a o parun pọ̀; iran awọn enia buburu li a o ké kuro. 39 Ṣugbọn lati ọwọ Oluwa wá ni igbala awọn olododo; on li àbo wọn ni igba ipọnju. 40 Oluwa yio si ràn wọn lọwọ, yio si gbà wọn, yio si gbà wọn lọwọ enia buburu, yio si gbà wọn la, nitoriti nwọn gbẹkẹle e.

Psalmu 38

Adura Ẹni tí Ìyà ń Jẹ

1 OLUWA, máṣe ba mi wi ninu ibinu rẹ: bẹ̃ni ki o máṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. 2 Nitori ti ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ rẹ si kì mi wọ̀ mọlẹ. 3 Kò si ibi yíyè li ara mi nitori ibinu rẹ; bẹ̃ni kò si alafia li egungun mi nitori ẹ̀ṣẹ mi. 4 Nitori ti ẹbi ẹ̀ṣẹ mi bori mi mọlẹ, bi ẹrù wuwo, o wuwo jù fun mi. 5 Ọgbẹ mi nrùn, o si dibajẹ nitori were mi. 6 Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ. 7 Nitoriti iha mi kún fun àrun ẹgbin; kò si si ibi yiyè li ara mi. 8 Ara mi hù, o si kan bajẹ; emi ti nkerora nitori aisimi aiya mi. 9 Oluwa, gbogbo ifẹ mi mbẹ niwaju rẹ; ikerora mi kò si pamọ́ kuro lọdọ rẹ. 10 Aiya mi nmi-hẹlẹ, agbara mi yẹ̀ mi silẹ: bi o ṣe ti imọlẹ oju mi ni, kò si lara mi. 11 Awọn olufẹ ati awọn ọrẹ mi duro li òkere kuro ni ìna mi, ati awọn ibatan mi duro li òkere rére. 12 Awọn pẹlu ti nwá ọkàn mi dẹkùn silẹ fun mi; ati awọn ti nwá ifarapa mi nsọ̀rọ ohun buburu, nwọn si ngbiro ẹ̀tan li gbogbo ọjọ. 13 Ṣugbọn emi, bi aditi, emi kò gbọ́; ati bi odi ti kò ya ẹnu rẹ̀. 14 Bẹ̃ni mo dabi ọkunrin ti kò gbọ́ran, ati li ẹnu ẹniti iyàn kò si. 15 Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi. 16 Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi. 17 Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi. 18 Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi. 19 Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i. 20 Awọn ti o si nfi buburu san rere li ọta mi; nitori emi ntọpa ohun ti iṣe rere. 21 Oluwa, máṣe kọ̀ mi silẹ; Ọlọrun mi, máṣe jina si mi. 22 Yara lati ran mi lọwọ, Oluwa igbala mi.

Psalmu 39

Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ

1 MO ni, emi o ma kiyesi ọ̀na mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ̀; emi o fi ijanu ko ara mi li ẹnu nigbati enia buburu ba mbẹ niwaju mi. 2 Mo fi idakẹ yadi, mo tilẹ pa ẹnu mi mọ́ kuro li ọ̀rọ rere: ibinujẹ mi si ru soke. 3 Aiya mi gbona ninu mi, nigbati emi nronu, ina ràn: nigbana ni mo fi ahọn mi sọ̀rọ. 4 Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin. 5 Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata. 6 Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ. 7 Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ. 8 Gbà mi ninu irekọja mi gbogbo: ki o má si sọ mi di ẹni ẹ̀gan awọn enia buburu. 9 Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e. 10 Mu ọwọ ìna rẹ kuro li ara mi: emi ṣegbe tan nipa ìja ọwọ rẹ. 11 Nigbati iwọ ba fi ibawi kilọ fun enia nitori ẹ̀ṣẹ, iwọ a ṣe ẹwà rẹ̀ a parun bi kòkoro aṣọ: nitõtọ asan li enia gbogbo. 12 Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri. 13 Da mi si, ki emi li agbara, ki emi ki o to lọ kuro nihinyi, ati ki emi ki o to ṣe alaisi.

Psalmu 40

Orin ìyìn

1 NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi. 2 O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ. 3 O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa. 4 Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke. 5 Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ. 6 Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère. 7 Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, emi de: ninu àpo-iwe nì li a gbe kọwe mi pe, 8 Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi. 9 Emi ti wãsu ododo ninu awujọ nla: kiyesi i, emi kò pa ete mi mọ́, Oluwa, iwọ mọ̀. 10 Emi kò fi ododo rẹ sin li aiya mi, emi o sọ̀rọ otitọ ati igbala rẹ: emi kò si pa iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ mọ́ kuro lọdọ ijọ nla nì. 11 Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo.

Adura Ìrànlọ́wọ́

12 Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi. 13 Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ, 14 Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si damu pọ̀, awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run; ki a lé wọn pada sẹhin, ki a si dojuti awọn ti nfẹ mi ni ibi. 15 Ki nwọn ki o di ofo fun ère itiju wọn, awọn ti nwi fun mi pe, A! a! 16 Ki gbogbo awọn ti nwá ọ, ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Gbigbega li Oluwa. 17 Ṣugbọn talaka ati alaini li emi; Oluwa si nṣe iranti mi; iwọ ni iranlọwọ mi ati olugbala mi: máṣe pẹ titi, Ọlọrun mi.

Psalmu 41

Adura Ẹni tí ń Ṣàìsàn

1 IBUKÚN ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni ìgbà ipọnju. 2 Oluwa yio pa a mọ́, yio si mu u wà lãye; a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ kì yio si fi i le ifẹ awọn ọta rẹ̀ lọwọ. 3 Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀. 4 Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ. 5 Awọn ọta mi nsọ ibi si mi pe, nigbawo ni on o kú, ti orukọ rẹ̀ yio si run? 6 Bi o ba si wá wò mi, on a ma sọ̀rọ ẹ̀tan: aiya rẹ̀ kó ẹ̀ṣẹ jọ si ara rẹ̀; nigbati o ba jade lọ, a ma wi i. 7 Gbogbo awọn ti o korira mi jumọ nsọ̀rọ kẹlẹ́ si mi: emi ni nwọn ngbìmọ ibi si. 8 Pe, ohun buburu li o dì mọ ọ ṣinṣin: ati ibiti o dubulẹ si, kì yio dide mọ. 9 Nitõtọ ọrẹ-iyọrẹ ara mi, ẹniti mo gbẹkẹle, ẹniti njẹ ninu onjẹ mi, o gbe gigisẹ rẹ̀ si mi. 10 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ṣãnu fun mi, ki o si gbé mi dide, ki emi ki o le san a fun wọn. 11 Nipa eyi ni mo mọ̀ pe iwọ ṣe oju-rere si mi, nitoriti awọn ọta mi kò yọ̀ mi. 12 Bi o ṣe ti emi ni, iwọ dì mi mu ninu ìwatitọ mi, iwọ si gbé mi kalẹ niwaju rẹ titi lai. 13 Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lailai titi lai. Amin, Amin.

IWE II

Psalmu 42

IWE KEJI

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 BI agbọnrin iti ma mi hẹlẹ si ipadò omi, Ọlọrun, bẹ̃li ọkàn mi nmi hẹlẹ si ọ. 2 Ongbẹ Ọlọrun ngbẹ ọkàn mi, ti Ọlọrun alãye: nigbawo li emi o wá, ti emi o si yọju niwaju Ọlọrun. 3 Omije mi li onjẹ mi li ọsan ati li oru, nigbati nwọn nwi fun mi nigbagbogbo pe, Ọlọrun rẹ dà? 4 Nigbati mo ba ranti nkan wọnyi, emi tú ọkàn mi jade ninu mi: emi ti ba ọ̀pọ ijọ enia lọ, emi ba wọn lọ si ile Ọlọrun, pẹlu ohùn ayọ̀ on iyìn, pẹlu ọ̀pọ enia ti npa ọjọ mimọ́ mọ́. 5 Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitori emi o sa ma yìn i sibẹ fun iranlọwọ oju rẹ̀. 6 Ọlọrun mi, ori ọkàn mi tẹ̀ ba ninu mi: nitorina li emi o ṣe ranti rẹ lati ilẹ Jordani wá, ati lati Hermoni, lati òke Misari wá. 7 Ibu omi npè ibu omi nipa hihó ṣiṣan-omi rẹ: gbogbo riru omi ati bibì omi rẹ bò mi mọlẹ. 8 Ṣugbọn Oluwa yio paṣẹ iṣeun-ifẹ rẹ̀ nigba ọ̀san, ati li oru orin rẹ̀ yio wà pẹlu mi, ati adura mi si Ọlọrun ẹmi mi. 9 Emi o wi fun Ọlọrun, apata mi pe, Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe mi? ẽṣe ti emi fi nrìn ni ìgbawẹ nitori inilara ọta nì. 10 Bi ẹnipe idà ninu egungun mi li ẹ̀gan ti awọn ọta mi ngàn mi; nigbati nwọn nwi fun mi lojojumọ pe, Ọlọrun rẹ dà? 11 Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun; nitori emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi ati Ọlọrun mi.

Psalmu 43

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 ṢE idajọ mi, Ọlọrun, ki o si gbà ọ̀ran mi rò si alailãnu orilẹ-ède: gbà mi lọwọ ẹlẹtan ati ọkunrin alaiṣõtọ nì. 2 Nitori iwọ li Ọlọrun agbara mi: ẽṣe ti iwọ fi ṣa mi tì? ẽṣe ti emi fi nrìn ni igbawẹ nitori inilara ọta nì. 3 Rán imọlẹ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki nwọn ki o ma ṣe amọna mi: ki nwọn ki o mu mi gùn òke mimọ́ rẹ, ati sinu agọ rẹ wọnni. 4 Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi. 5 Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi.

Psalmu 44

Adura Ààbò

1 ỌLỌRUN, awa ti fi eti wa gbọ́, awọn baba wa si ti sọ fun wa ni iṣẹ́ nla ti iwọ ṣe li ọjọ wọn, ni igbà àtijọ́. 2 Bi iwọ ti fi ọwọ rẹ lé awọn keferi jade, ti iwọ si gbin wọn: bi iwọ ti fõró awọn enia na, ti iwọ si mu wọn gbilẹ. 3 Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn. 4 Iwọ li Ọba mi, Ọlọrun: paṣẹ igbala fun Jakobu. 5 Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ. 6 Nitoriti emi kì yio gbẹkẹle ọrun mi, bẹ̃ni idà mi kì yio gbà mi. 7 Ṣugbọn iwọ li o ti gbà wa lọwọ awọn ọta wa, iwọ si ti dojutì awọn ti o korira wa. 8 Niti Ọlọrun li awa nkọrin iyìn li ọjọ gbogbo, awa si nyìn orukọ rẹ lailai. 9 Ṣugbọn iwọ ti ṣa wa tì, iwọ si ti dojutì wa: iwọ kò si ba ogun wa jade lọ. 10 Iwọ mu wa pẹhinda fun ọta wa: ati awọn ti o korira wa nṣe ikogun fun ara wọn. 11 Iwọ ti fi wa fun jijẹ bi ẹran agutan; iwọ si ti tú wa ka ninu awọn keferi. 12 Iwọ ti tà awọn enia rẹ li asan, iwọ kò si fi iye-owo wọn sọ ọrọ̀ rẹ di pupọ. 13 Iwọ sọ wa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣutì-si, si awọn ti o yi ni ka. 14 Iwọ sọ wa di ẹni-owe ninu awọn orilẹ-ède, ati imirisi ninu awọn enia. 15 Idamu mi mbẹ niwaju mi nigbagbogbo, itiju mi si bò mi mọlẹ. 16 Nitori ohùn ẹniti ngàn, ti o si nsọ̀rọ buburu; nitori ipa ti ọta olugbẹsan nì. 17 Gbogbo wọnyi li o de si wa; ṣugbọn awa kò gbagbe rẹ, bẹ̃li awa kò ṣe eke si majẹmu rẹ. 18 Aiya wa kò pada sẹhin, bẹ̃ni ìrin wa kò yà kuro ni ipa tirẹ; 19 Bi iwọ tilẹ ti fọ́ wa bajẹ ni ibi awọn ikõkò, ti iwọ si fi ojiji ikú bò wa mọlẹ. 20 Bi o ba ṣepe awa gbagbe orukọ Ọlọrun wa, tabi bi awa ba nà ọwọ wa si ọlọrun ajeji; 21 Njẹ Ọlọrun ki yio ri idi rẹ̀? nitori o mọ̀ ohun ìkọkọ aiya. 22 Nitõtọ, nitori rẹ li a ṣe npa wa kú ni gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa. 23 Ji! ẽṣe ti iwọ nsùn, Oluwa? dide, máṣe ṣa wa tì kuro lailai. 24 Ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́, ti iwọ si fi gbagbe ipọnju wa ati inira wa? 25 Nitoriti a tẹri ọkàn wa ba sinu ekuru: inu wa dì mọ erupẹ ilẹ. 26 Dide fun iranlọwọ wa, ki o si rà wa pada nitori ãnu rẹ.

Psalmu 45

Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba

1 AIYA mi nhumọ̀ ọ̀ran rere: emi nsọ ohun ti mo ti ṣe, fun ọba ni: kalamu ayawọ akọwe li ahọn mi. 2 Iwọ yanju jù awọn ọmọ enia lọ: a dà ore-ọfẹ si ọ li ète: nitorina li Ọlọrun nbukún fun ọ lailai. 3 San idà rẹ mọ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-nla rẹ. 4 Ati ninu ọlánlá rẹ ma gẹṣin lọ li alafia, nitori otitọ ati ìwa-tutu ati ododo; ọwọ ọtún rẹ yio si kọ́ ọ li ohun ẹ̀ru. 5 Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ. 6 Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni. 7 Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ. 8 Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀. 9 Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri. 10 Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ! 11 Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i. 12 Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ. 13 Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀. 14 Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ̀ ọba wá: awọn wundia, ẹgbẹ rẹ̀ ti ntọ̀ ọ lẹhin li a o mu tọ̀ ọ wá. 15 Pẹlu inu didùn ati pẹlu ayọ̀ li a o fi mu wọn wá: nwọn o si wọ̀ ãfin ọba lọ. 16 Nipò awọn baba rẹ li awọn ọmọ rẹ yio wà, ẹniti iwọ o ma fi jẹ oye lori ilẹ gbogbo. 17 Emi o ma ṣe orukọ rẹ ni iranti ni iran gbogbo: nitorina li awọn enia yio ṣe ma yìn ọ lai ati lailai.

Psalmu 46

Ọlọrun Wà pẹlu Wa

1 ỌLỌRUN li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju. 2 Nitorina li awa kì yio bẹ̀ru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn oke nla nipò lọ si inu okun: 3 Bi omi rẹ̀ tilẹ nho ti o si nru, bi awọn òke nla tilẹ nmì nipa ọwọ bibì rẹ̀. 4 Odò nla kan wà, ṣiṣan eyiti yio mu inu ilu Ọlọrun dùn, ibi mimọ́ agọ wọnni ti Ọga-ogo. 5 Ọlọrun mbẹ li arin rẹ̀; a kì yio ṣi i ni idi: Ọlọrun yio ràn a lọwọ ni kutukutu owurọ. 6 Awọn keferi nbinu, awọn ilẹ ọba ṣidi: o fọhun rẹ̀, aiye yọ́. 7 Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa. 8 Ẹ wá wò awọn iṣẹ Oluwa, iru ahoro ti o ṣe ni aiye. 9 O mu ọ̀tẹ tan de opin aiye; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ meji; o si fi kẹkẹ́ ogun jona. 10 Ẹ duro jẹ, ki ẹ si mọ̀ pe emi li Ọlọrun, a o gbé mi ga ninu awọn keferi, a o gbé mi ga li aiye. 11 Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.

Psalmu 47

Ọba Àwọn Ọba

1 ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun. 2 Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo. 3 On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa. 4 On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ. 5 Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè. 6 Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn. 7 Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn. 8 Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀. 9 Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ.

Psalmu 48

OLUWA Tóbi

1 ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀. 2 Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla. 3 A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀. 4 Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ. 5 Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ. 6 Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi. 7 Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi. 8 Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai. 9 Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ. 10 Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo. 11 Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ. 12 Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀. 13 Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin. 14 Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.

Psalmu 49

Ìwà Òmùgọ̀ ni Igbẹkẹ le Ọrọ̀

1 ẸGBỌ́ eyi, gbogbo enia; ẹ fi eti si i, gbogbo ẹnyin araiye: 2 Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu. 3 Ẹnu mi yio sọ̀rọ ọgbọ́n, ati iṣaro aiya mi yio jẹ oye. 4 Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru. 5 Ẽṣe ti emi o fi bẹ̀ru li ọjọ ibi, nigbati ẹ̀ṣẹ awọn ajinilẹsẹ mi yi mi ka. 6 Awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ wọn, ti nwọn si nṣe ileri li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ wọn; 7 Kò si ẹnikan, bi o ti wù ki o ṣe, ti o le rà arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò le san owo-irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀. 8 Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai: 9 Nipe ki o fi mã wà lailai, ki o má ṣe ri isa-okú. 10 Nitori o nri pe awọn ọlọgbọ́n nkú, bẹ̃li aṣiwere ati ẹranko enia nṣegbe, nwọn si nfi ọrọ̀ wọn silẹ fun ẹlomiran. 11 Ìro inu wọn ni, ki ile wọn ki o pẹ titi lai, ati ibujoko wọn lati irandiran; nwọn sọ ilẹ wọn ní orukọ ara wọn. 12 Ṣugbọn enia ti o wà ninu ọlá kò duro pẹ: o dabi ẹranko ti o ṣegbé. 13 Ipa ọ̀na wọn yi ni igbẹkẹle wọn: ọ̀rọ wọn si tọ́ li oju awọn ọmọ wọn. 14 Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn. 15 Ṣugbọn Ọlọrun ni yio rà ọkàn mi lọwọ isa-okú: nitoripe on o gbà mi. 16 Iwọ máṣe bẹ̀ru, nitori ẹnikan di ọlọrọ̀, nitori iyìn ile rẹ̀ npọ̀ si i. 17 Nitoripe, igbati o ba kú, kì yio kó ohun kan lọ: ogo rẹ̀ kì yio sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ. 18 Nigbati o wà lãye bi o tilẹ nsure fun ọkàn ara rẹ̀: ti awọn enia nyìn ọ, nigbati iwọ nṣe rere fun ara rẹ. 19 Ọkàn yio lọ si ọdọ iran awọn baba rẹ̀; nwọn kì yio ri imọlẹ lailai. 20 Ọkunrin ti o wà ninu ọlá, ti kò moye, o dabi ẹranko ti o ṣegbe.

Psalmu 50

Ìsìn Tòótọ́

1 ỌLỌRUN Olodumare, ani Oluwa li o ti sọ̀rọ, o si pè aiye lati ìla-õrun wá titi o fi de ìwọ rẹ̀. 2 Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ. 3 Ọlọrun wa mbọ̀, kì yio si dakẹ; iná yio ma jó niwaju rẹ̀, ẹfufu lile yio si ma ja yi i ka kiri. 4 Yio si kọ si awọn ọrun lati òke wá, ati si aiye, ki o le ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀. 5 Kó awọn enia mimọ́ mi jọ pọ̀ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu. 6 Awọn ọrun yio si sọ̀rọ ododo rẹ̀: nitori Ọlọrun tikararẹ̀ li onidajọ. 7 Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si sọ̀rọ; Israeli, emi o si jẹri si ọ: emi li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ. 8 Emi kì yio ba ọ wi nitori ẹbọ rẹ, ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ wà niwaju mi nigbagbogbo. 9 Emi kì yio mu akọ-malu lati ile rẹ jade, tabi obukọ ninu agbo-ẹran rẹ: 10 Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke. 11 Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi. 12 Bi ebi npa mi, emi kì yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rẹ̀. 13 Emi o ha jẹ ẹran malu, tabi emi a ma mu ẹ̀jẹ ewurẹ bi? 14 Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo. 15 Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo. 16 Ṣugbọn Ọlọrun wi fun enia buburu pe, Kini iwọ ni ifi ṣe lati ma sọ̀rọ ilana mi, tabi ti iwọ fi nmu majẹmu mi li ẹnu rẹ? 17 Wò o, iwọ sa korira ẹkọ́, iwọ si ti ṣá ọ̀rọ mi tì lẹhin rẹ. 18 Nigbati iwọ ri olè, nigbana ni iwọ ba a mọ̀ ọ pọ̀, iwọ si ba awọn àgbere ṣe ajọpin. 19 Iwọ fi ẹnu rẹ fun buburu, ati ahọn rẹ npete ẹ̀tan. 20 Iwọ joko, iwọ si sọ̀rọ si arakunrin rẹ: iwọ mba orukọ ọmọ iya rẹ jẹ. 21 Nkan wọnyi ni iwọ ṣe emi si dakẹ; iwọ ṣebi emi tilẹ dabi iru iwọ tikararẹ; emi o ba ọ wi, emi o si kà wọn li ẹsẹ-ẹsẹ ni oju rẹ. 22 Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ti kò si olugbala. 23 Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyìn, o yìn mi logo: ati ẹniti o ba mu ọ̀na ọ̀rọ rẹ̀ tọ́ li emi o fi igbala Ọlọrun hàn fun.

Psalmu 51

Adura Ìdáríjì

1 ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ: gẹgẹ bi ìrọnu ọ̀pọ ãnu rẹ, nù irekọja mi nù kuro. 2 Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. 3 Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigbagbogbo li ẹ̀ṣẹ mi si mbẹ niwaju mi. 4 Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ lare, nigbati iwọ ba nsọ̀rọ, ki ara rẹ ki o le mọ́, nigbati iwọ ba nṣe idajọ. 5 Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi. 6 Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n. 7 Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ. 8 Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀. 9 Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi, ki iwọ ki o si nù gbogbo aiṣedede mi nù kuro. 10 Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi. 11 Máṣe ṣa mi tì kuro niwaju rẹ; ki o má si ṣe gbà Ẹmi mimọ́ rẹ lọwọ mi. 12 Mu ayọ̀ igbala rẹ pada tọ̀ mi wá; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbé mi duro. 13 Nigbana li emi o ma kọ́ awọn olurekọja li ọ̀na rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yio si ma yipada si ọ. 14 Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan. 15 Oluwa, iwọ ṣi mi li ète; ẹnu mi yio si ma fi iyìn rẹ han: 16 Nitori iwọ kò fẹ ẹbọ, ti emi iba ru u: inu rẹ kò dùn si ọrẹ-ẹbọ sisun. 17 Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ kì yio gàn. 18 Ṣe rere ni didùn inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalemu. 19 Nigbana ni inu rẹ yio dùn si ẹbọ ododo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọ̀tọtọ ọrẹ-ẹbọ sisun: nigbana ni nwọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ.

Psalmu 52

Ìdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun

1 ẼṢE ti iwọ fi nṣe-fefe ninu ìwa-ìka, iwọ alagbara ọkunrin? ore Ọlọrun duro pẹ titi. 2 Ahọn rẹ ngberò ìwa-ìka; bi abẹ mimú o nṣiṣẹ ẹ̀tan. 3 Iwọ fẹ ibi jù ire lọ; ati eke jù ati sọ ododo lọ. 4 Iwọ fẹ ọ̀rọ ipanirun gbogbo, iwọ ahọn ẹ̀tan. 5 Ọlọrun yio si lù ọ bolẹ lailai, yio si dì ọ mu, yio si ja ọ kuro ni ibujoko rẹ, yio si fà ọ tu kuro lori ilẹ alãye. 6 Olododo yio ri i pẹlu, yio si bẹ̀ru, yio si ma rẹrin rẹ̀ pe, 7 Kiyesi ọkunrin ti kò fi Ọlọrun ṣe agbara rẹ̀; bikoṣe li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ li o gbẹkẹle, o si mu ara rẹ̀ le ninu ìwa buburu rẹ̀. 8 Ṣugbọn emi dabi igi olifi tutu ni ile Ọlọrun: emi gbẹkẹle ãnu Ọlọrun lai ati lailai. 9 Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ́ rẹ.

Psalmu 53

Èrè Òmùgọ̀

1 AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ nwọn si nṣe irira ẹ̀ṣẹ: kò si ẹniti o nṣe rere. 2 Ọlọrun bojuwo ilẹ lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun. 3 Gbogbo wọn li o si pada sẹhin, nwọn si di elẽri patapata: kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan. 4 Awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ko ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun: nwọn kò si kepe Ọlọrun. 5 Nibẹ ni nwọn gbe wà ni ibẹ̀ru nla nibiti ẹ̀ru kò gbe si: nitori Ọlọrun ti fún egungun awọn ti o dótì ọ ka: iwọ ti dojutì wọn, nitori Ọlọrun ti kẹgàn wọn. 6 Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá? Nigbati Ọlọrun ba mu igbekun awọn enia rẹ̀ pada wá, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.

Psalmu 54

Adura Ààbò

1 ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ. 2 Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi. 3 Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn. 4 Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro. 5 Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ. 6 Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara. 7 Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi.

Psalmu 55

Adura Ẹni tí Ọ̀rẹ́ Dà

1 FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi. 2 Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo; 3 Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi. 4 Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi. 5 Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ. 6 Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi. 7 Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju. 8 Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na. 9 Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na. 10 Ọsan ati oru ni nwọn fi nrìn odi rẹ̀ kiri: ìwa-ika pẹlu ati ikãnu mbẹ li arin rẹ̀. 11 Ìwa buburu mbẹ li arin rẹ̀: ẹ̀tan ati eke kò kuro ni igboro rẹ̀. 12 Nitoriti kì iṣe ọta li o gàn mi: njẹ emi iba pa a mọra: bẹ̃ni kì iṣe ẹniti o korira mi li o gbé ara rẹ̀ ga si mi; njẹ emi iba fi ara mi pamọ́ kuro lọdọ rẹ̀: 13 Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi. 14 Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ. 15 Ki ikú ki o dì wọn mu, ki nwọn ki o si lọ lãye si isa-okú: nitori ti ìwa buburu mbẹ ni ibujoko wọn, ati ninu wọn. 16 Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepè Ọlọrun; Oluwa yio si gbà mi. 17 Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi. 18 O ti gbà ọkàn mi silẹ li alafia lọwọ ogun ti o ti dó tì mi: nitoripe pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ni nwọn dide si mi. 19 Ọlọrun yio gbọ́, yio si pọ́n wọn loju, ani ẹniti o ti joko lati igbani. Nitoriti nwọn kò ni ayipada, nwọn kò si bẹ̀ru Ọlọrun. 20 O ti nà ọwọ rẹ̀ si iru awọn ti o wà li alafia pẹlu rẹ̀: o ti dà majẹmu rẹ̀. 21 Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ kunna jù ori-amọ lọ, ṣugbọn ogun jija li o wà li aiya rẹ̀: ọ̀rọ rẹ̀ kunna jù ororo lọ, ṣugbọn idà fifayọ ni nwọn. 22 Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa, on ni yio si mu ọ duro: on kì yio jẹ ki ẹsẹ olododo ki o yẹ̀ lai. 23 Ṣugbọn iwọ, Ọlọrun, ni yio mu wọn sọkalẹ lọ si iho iparun: awọn enia ẹ̀jẹ ati enia ẹ̀tan kì yio pe àbọ ọjọ wọn; ṣugbọn emi o gbẹkẹle ọ.

Psalmu 56

Adura Igbẹkẹ le Ọlọrun

1 ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi: nitoriti enia nfẹ gbe mi mì; o mba mi jà lojojumọ, o nni mi lara. 2 Awọn ọta mi nfẹ igbe mi mì lojojumọ: nitori awọn ti nfi igberaga ba mi ja pọ̀. 3 Nigbati ẹ̀ru ba mbà mi, emi o gbẹkẹle ọ. 4 Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀, Ọlọrun li emi o gbẹkẹ mi le, emi kì yio bèru: kili ẹran-ara le ṣe si mi. 5 Lojojumọ ni nwọn nlọ́ ọ̀rọ mi: ibi ni gbogbo ìro inu wọn si mi: 6 Nwọn kó ara wọn jọ, nwọn ba, nwọn kiyesi ìrin mi, nwọn ti nṣọ̀na ọkàn mi. 7 Nwọn ha le ti ipa aiṣedede là? ni ibinu, bi awọn enia na lulẹ̀, Ọlọrun. 8 Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi? 9 Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi. 10 Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀: nipa Oluwa li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀. 11 Ọlọrun li emi gbẹkẹ mi le, emi kì yio bẹ̀ru kili enia le ṣe si mi. 12 Ẹjẹ́ rẹ mbẹ lara mi, Ọlọrun: emi o fi iyìn fun ọ. 13 Nitoripe iwọ li o ti gbà ọkàn mi lọwọ ikú: iwọ ki yio ha gbà ẹsẹ mi lọwọ iṣubu? ki emi ki o le ma rìn niwaju Ọlọrun ni imọlẹ awọn alãye?

Psalmu 57

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 ṢÃNU fun mi: Ọlọrun, ṣãnu fun mi: nitoriti ọkàn mi gbẹkẹle ọ: lõtọ, li ojiji iyẹ-apa rẹ li emi o fi ṣe àbo mi, titi wahala wọnyi yio fi rekọja. 2 Emi o kigbe pe Ọlọrun Ọga-ogo; si Ọlọrun ti o ṣe ohun gbogbo fun mi. 3 On o ranṣẹ lati ọrun wá, yio si gbà mi bi ẹniti nfẹ gbe mi mì tilẹ nkẹgàn mi. Ọlọrun yio rán ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ jade. 4 Ọkàn mi wà lãrin awọn kiniun: emi tilẹ dubulẹ lãrin awọn ti o gbiná, eyinì ni awọn ọmọ enia, ehín ẹniti iṣe ọ̀kọ ati ọfa, ati ahọn wọn, idà mimú. 5 Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù ọrun lọ; ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ. 6 Nwọn ti ta àwọn silẹ fun ẹsẹ mi: nwọn tẹ ori ọkàn mi ba: nwọn ti wà iho silẹ niwaju mi, li ãrin eyina li awọn tikarawọn jìn si. 7 Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyìn. 8 Jí, iwọ ogo mi; jí, ohun-èlo orin ati duru: emi tikarami yio si jí ni kutukutu. 9 Emi o ma yìn ọ, Oluwa lãrin awọn enia: emi o si ma kọrin si ọ lãrin awọn orilẹ-ède. 10 Nitoriti ãnu rẹ pọ̀ de ọrun, ati otitọ rẹ de awọsanma. 11 Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.

Psalmu 58

Kí Ọlọrun jẹ Ìkà níyà

1 ẸNYIN ha nsọ ododo nitõtọ, ẹnyin ijọ enia? ẹnyin ha nṣe idajọ ti o ṣe titọ, ẹnyin ọmọ enia? 2 Nitõtọ, ẹnyin nṣiṣẹ buburu li aiya; ẹnyin nwọ̀n ìwa-agbara ọwọ nyin li aiye. 3 Lati inu iya wọn wá li awọn enia buburu ti ṣe iyapa: nwọn ti ṣina lojukanna ti a ti bi wọn, nwọn a ma ṣeke. 4 Oró wọn dabi oró ejò: nwọn dabi aditi ejò pamọlẹ ti o di ara rẹ̀ li eti; 5 Ti kò fẹ igbọ́ ohùn awọn atuniloju, bi o ti wù ki o ma fi ọgbọ́n ṣe ituju to. 6 Ká wọn li ehin, Ọlọrun, li ẹnu wọn: ká ọ̀gan awọn ọmọ kiniun nì, Oluwa. 7 Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja. 8 Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn. 9 Ki ikoko nyin ki o to mọ̀ igbona ẹgún, iba tutu iba ma jo, yio fi iji gbá wọn lọ. 10 Olododo yio yọ̀ nigbati o ba ri ẹsan na: yio si wẹ̀ ẹsẹ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ awọn enia buburu. 11 Bẹ̃li enia o si wipe, Lõtọ, ère mbẹ fun olododo: lõtọ, on li Ọlọrun ti o nṣe idajọ ni aiye.

Psalmu 59

Adura Ààbò

1 ỌLỌRUN mi, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: dãbobo mi lọwọ awọn ti o dide si mi. 2 Gbà mi lọwọ awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ki o si gbà mi silẹ lọwọ awọn enia-ẹ̀jẹ. 3 Sa kiyesi i, nwọn ba ni buba fun ọkàn mi, awọn alagbara pejọ si mi; kì iṣe nitori irekọja mi, tabi nitori ẹ̀ṣẹ mi, Oluwa. 4 Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i. 5 Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni. 6 Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka. 7 Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́? 8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi. 9 Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi. 10 Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi. 11 Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa. 12 Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe. 13 Run wọn ni ibinu, run wọn, ki nwọn ki o má ṣe si mọ́: ki o si jẹ ki nwọn ki o mọ̀ pe, Ọlọrun li olori ni Jakobu titi o fi de opin aiye. 14 Ati li aṣalẹ jẹ ki nwọn ki o pada; ki nwọn ki o pariwo bi ajá, ki nwọn ki o si ma yi ilu na ka kiri. 15 Jẹ ki nwọn ki o ma rìn soke rìn sodò fun ohun jijẹ, bi nwọn kò ba yó, nwọn o duro ni gbogbo oru na. 16 Ṣugbọn emi o kọrin agbara rẹ; nitõtọ, emi o kọrin ãnu rẹ kikan li owurọ: nitori pe iwọ li o ti nṣe àbo ati ibi-asala mi li ọjọ ipọnju mi. 17 Iwọ, agbara mi, li emi o kọrin si: nitori Ọlọrun li àbo mi, Ọlọrun ánu mi!

Psalmu 60

Adura fún Ìgbàlà

1 ỌLỌRUN, iwọ ti ṣa wa tì, iwọ ti tú wa ka, inu rẹ ti bajẹ; tún ara rẹ yipada si wa. 2 Iwọ ti mu ilẹ warìri; iwọ ti fọ ọ: mu fifọ rẹ̀ bọ̀ sipò: nitoriti o nmì. 3 Iwọ ti fi ohun ti o ṣoro hàn awọn enia rẹ: iwọ mu wa mu ọti-waini itagbọngbọn. 4 Iwọ ti fi ọpagun fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ, ki a le ma fi i hàn nitori otitọ. 5 Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là; fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si gbohùn mi. 6 Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu. 7 Ti emi ni Gileadi, ti emi ni Manasse; Efraimu pẹlu li agbara ori mi; Juda li olofin mi; 8 Moabu li ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bàta mi si: Filistia ma ho iho ayọ̀ fun mi! 9 Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi nì? tani yio sin mi lọ si Edomu? 10 Iwọ ha kọ́, Ọlọrun, ẹniti o ṣa wa tì? ati iwọ, Ọlọrun, ti kò ba ogun wa jade lọ? 11 Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori pe asan ni iranlọwọ enia. 12 Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin: nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.

Psalmu 61

Adura Ààbò

1 GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi. 2 Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ. 3 Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì. 4 Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ. 5 Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi. 6 Iwọ o fa ẹmi ọba gùn: ati ọjọ ọdun rẹ̀ bi atiran-diran. 7 On o ma gbe iwaju Ọlọrun lailai; pèse ãnu ati otitọ, ti yio ma ṣe itọju rẹ̀. 8 Bẹ̃li emi o ma kọrin iyìn si orukọ rẹ lailai, ki emi ki o le ma san ẹjẹ́ mi li ojojumọ.

Psalmu 62

Ọlọrun ni Ààbò Wa

1 ỌLỌRUN nikan li ọkàn mi duro jẹ dè; lati ọdọ rẹ̀ wá ni igbala mi. 2 On nikan li apata mi ati igbala mi; on li àbo mi, emi kì yio ṣipò pada jọjọ. 3 Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ. 4 Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn. 5 Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi. 6 On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò. 7 Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun. 8 Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa. 9 Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ. 10 Máṣe gbẹkẹle inilara, ki o má si ṣe gberaga li olè jija: bi ọrọ̀ ba npọ̀ si i, máṣe gbe ọkàn nyin le e. 11 Ọlọrun ti sọ̀rọ lẹ̃kan; lẹ̃rinkeji ni mo gbọ́ eyi pe: ti Ọlọrun li agbara. 12 Pẹlupẹlu, Oluwa, tirẹ li ãnu: nitoriti iwọ san a fun olukulùku enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.

Psalmu 63

Wíwá Ọlọrun

1 ỌLỌRUN, iwọ li Ọlọrun mi; ni kutukutu li emi o ma ṣafẹri rẹ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran-ara mi fà si ọ ni ilẹ gbigbẹ, ati ilẹ ti npongbẹ, nibiti omi kò gbe si. 2 Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ. 3 Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ. 4 Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ. 5 Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ: 6 Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru. 7 Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀. 8 Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró. 9 Ṣugbọn awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run, nwọn o lọ si iha isalẹ-ilẹ. 10 Nwọn o ti ọwọ idà ṣubu: nwọn o si ṣe ijẹ fun kọ̀lọkọlọ. 11 Ṣugbọn ọba yio ma yọ̀ ninu Ọlọrun; olukuluku ẹniti o nfi i bura ni yio ṣogo: ṣugbọn awọn ti nṣeke li a o pa li ẹnu mọ́.

Psalmu 64

Adura Ààbò

1 ỌLỌRUN, gbohùn mi ninu aroye mi: pa ẹmi mi mọ́ lọwọ ẹ̀ru ọta nì. 2 Pa mi mọ́ lọwọ ìmọ ìkọkọ awọn enia buburu: lọwọ irukerudo awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. 3 Ẹniti npọ̀n ahọn wọn bi ẹnipe idà, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, ani ọ̀rọ kikoro: 4 Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru. 5 Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn? 6 Nwọn gbero ẹ̀ṣẹ; nwọn wipe, awa ti pari ero ti a gbà tan: ati ìro inu olukuluku wọn, ati aiya wọn, o jinlẹ. 7 Ṣugbọn Ọlọrun yio tafà si wọn lojiji; nwọn o si gbọgbẹ. 8 Bẹ̃ni ahọn wọn yio mu wọn ṣubu lu ara wọn: gbogbo ẹniti o ri wọn yio mì ori wọn. 9 Ati gbogbo enia ni yio ma bẹ̀ru, nwọn o si ma sọ̀rọ iṣẹ Ọlọrun; nitoriti nwọn o fi ọgbọ́n rò iṣẹ rẹ̀. 10 Olododo yio ma yọ̀ nipa ti Oluwa, yio si ma gbẹkẹle e; ati gbogbo ẹni-iduro-ṣinṣin li aiya ni yio ma ṣogo.

Psalmu 65

Ìyìn ati Ọpẹ́

1 ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ. 2 Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀. 3 Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro. 4 Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ. 5 Ohun iyanu nipa ododo ni iwọ fi da wa lohùn, Ọlọrun igbala wa: ẹniti iṣe igbẹkẹle gbogbo opin aiye, ati awọn ti o jina réré si okun. 6 Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure: 7 Ẹniti o pa ariwo okun mọ́ rọrọ, ariwo riru-omi wọn, ati gìrìgìrì awọn enia. 8 Awọn pẹlu ti ngbe apa ipẹkun mbẹ̀ru nitori àmi rẹ wọnni: iwọ mu ijade owurọ ati ti aṣalẹ yọ̀. 9 Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃. 10 Iwọ fi irinmi si aporo rẹ̀ pipọpìpọ: iwọ si tẹ́ ogulutu rẹ̀: iwọ fi ọwọ òjọ mu ilẹ rẹ̀ rọ̀: iwọ busi hihu rẹ̀. 11 Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkán ni ipa-ọ̀na rẹ. 12 Papa-tutù aginju nkán: awọn òke kekèke fi ayọ̀ di ara wọn li àmure. 13 Agbo ẹran li a fi wọ̀ pápá-tútù na li aṣọ: afonifoji li a fi ọka bò mọlẹ: nwọn nhó fun ayọ̀, nwọn nkọrin pẹlu.

Psalmu 66

Orin Ìyìn ati Ọpẹ́

1 Ẹ hó iho ayọ̀ si Ọlọrun, ẹnyin ilẹ gbogbo: 2 Ẹ kọrin ọlá orukọ rẹ̀: ẹ mu iyìn rẹ̀ li ogo. 3 Ẹ wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti li ẹ̀ru to ninu iṣẹ rẹ! nipa ọ̀pọ agbara rẹ li awọn ọta rẹ yio fi ori wọn balẹ fun ọ. 4 Gbogbo aiye ni yio ma sìn ọ, nwọn o si ma kọrin si ọ; nwọn o ma kọrin si orukọ rẹ. 5 Ẹ wá wò iṣẹ Ọlọrun, o li ẹ̀ru ni iṣe rẹ̀ si awọn ọmọ enia. 6 O sọ okun di ilẹ gbigbẹ: nwọn fi ẹsẹ là odò já: nibẹ li awa gbe yọ̀ ninu rẹ̀. 7 O jọba nipa agbara rẹ̀ lailai; oju rẹ̀ nwò awọn orilẹ-ède: ki awọn ọlọtẹ ki o máṣe gbé ara wọn ga. 8 Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun wa, ẹnyin enia, ki ẹ si mu ni gbọ́ ohùn iyìn rẹ̀. 9 Ẹniti o mu ẹmi wa wà lãye, ti kò si jẹ ki ẹsẹ wa ki o yẹ̀. 10 Ọlọrun, nitori ti iwọ ti ridi wa: iwọ ti dan wa wò, bi ã ti idan fadaka wò. 11 Iwọ mu wa wọ̀ inu àwọn; iwọ fi ipọnju le wa li ẹgbẹ. 12 Iwọ mu awọn enia gùn wa li ori: awa nwọ inu iná ati omi lọ, ṣugbọn iwọ mu wa jade wá si ibi irọra. 13 Emi o lọ sinu ile rẹ ti emi ti ẹbọ sisun: emi o san ẹjẹ́ mi fun ọ, 14 Ti ète mi ti jẹ́, ti ẹnu si ti sọ, nigbati mo wà ninu ipọnju. 15 Emi o ru ẹbọ sisun ọlọra si ọ, pẹlu õrùn ọrá àgbo; emi o rubọ akọ-malu pẹlu ewurẹ. 16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, emi o sọ ohun ti o ṣe fun ọkàn mi. 17 Emi fi ẹnu mi kigbe pè e, emi o si fi àhọn mi buyin fun u. 18 Bi emi ba gbà ẹ̀ṣẹ li aiya mi, Oluwa kì yio gbohùn mi: 19 Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun ti gbohùn mi: o si ti fi eti si ohùn adura mi. 20 Olubukún li Ọlọrun, ti kò yi adura mi pada kuro, tabi ãnu rẹ̀ kuro lọdọ mi.

Psalmu 67

Orin Ọpẹ́

1 KI Ọlọrun ki o ṣãnu fun wa, ki o si busi i fun wa; ki o si ṣe oju rẹ̀ ki o mọlẹ si wa lara, 2 Ki ọ̀na rẹ ki o le di mimọ̀ li aiye, ati igbala ilera rẹ ni gbogbo orilẹ-ède. 3 Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ. 4 Jẹ ki inu awọn orilẹ-ède ki o dùn, ki nwọn ki o ma kọrin fun ayọ̀: nitoriti iwọ o fi ododo ṣe idajọ enia, iwọ o si jọba awọn orilẹ-ède li aiye. 5 Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ. 6 Nigbana ni ilẹ yio to ma mu asunkún rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tikararẹ̀ yio busi i fun wa. 7 Ọlọrun yio busi i fun wa; ati gbogbo opin aiye yio si ma bẹ̀ru rẹ̀.

Psalmu 68

Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè

1 KI Ọlọrun ki o dide, ki a si tú awọn ọta rẹ̀ ka: ki awọn ti o korira rẹ̀ pẹlu, ki nwọn ki o salọ kuro niwaju rẹ̀. 2 Bi ẽfin ti ifẹ lọ, bẹ̃ni ki o fẹ́ wọn lọ; bi ida ti iyọ́ niwaju iná, bẹ̃ni ki enia buburu ki o ṣegbe niwaju Ọlọrun. 3 Ṣugbọn jẹ ki inu awọn olododo ki o dùn; ki nwọn ki o yọ̀ niwaju Ọlọrun. nitõtọ, ki nwọn ki o yọ̀ gidigidi. 4 Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹ kọrin iyin si orukọ rẹ̀: ẹ la ọ̀na fun ẹniti nrekọja li aginju nipa JAH, orukọ rẹ̀, ki ẹ si ma yọ̀ niwaju rẹ̀. 5 Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́. 6 Ọlọrun mu ẹni-ofo joko ninu ile: o mu awọn ti a dè li ẹ̀wọn jade wá si irọra: ṣugbọn awọn ọlọtẹ ni ngbe inu ilẹ gbigbẹ. 7 Ọlọrun, nigbati iwọ jade lọ niwaju awọn enia rẹ, nigbati iwọ nrìn lọ larin aginju. 8 Ilẹ mì, ọrun bọ silẹ niwaju Ọlọrun: ani Sinai tikararẹ̀ mì niwaju Ọlọrun, Ọlọrun Israeli. 9 Ọlọrun, iwọ li o rán ọ̀pọlọpọ òjo si ilẹ-ini rẹ, nigbati o rẹ̀ ẹ tan, iwọ tù u lara. 10 Ijọ enia rẹ li o tẹ̀do sinu rẹ̀: iwọ Ọlọrun ninu ore rẹ li o ti pèse fun awọn talaka. 11 Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀: 12 Awọn ọba awọn ẹgbẹ ogun sa, nwọn sa lọ: obinrin ti o si joko ni ile ni npin ikogun na. 13 Nigbati ẹnyin dubulẹ larin agbo ẹran, nigbana ni ẹnyin o dabi iyẹ adaba ti a bò ni fadaka, ati ìyẹ́ rẹ̀ pẹlu wura pupa. 14 Nigbati Olodumare tú awọn ọba ká ninu rẹ̀, o dabi òjo-didì ni Salmoni. 15 Òke Ọlọrun li òke Baṣani: òke ti o ni ori pupọ li òke Baṣani. 16 Ẽṣe ti ẹnyin nfi ilara wò, ẹnyin òke, òke na ti Ọlọrun fẹ lati ma gbe? nitõtọ, Oluwa yio ma gbe ibẹ lailai. 17 Ainiye ni kẹkẹ́ ogun Ọlọrun, ani ẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun: Oluwa mbẹ larin wọn, ni Sinai ni ibi mimọ́ nì. 18 Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe. 19 Olubukún li Oluwa, ẹni ti o nba wa gbé ẹrù wa lojojumọ; Ọlọrun ni igbala wa. 20 Ẹniti iṣe Ọlọrun wa li Ọlọrun igbala; ati lọwọ Jehofah Oluwa, li amúwa lọwọ ikú wà. 21 Nitori Ọlọrun yio fọ ori awọn ọta rẹ̀, ati agbari onirun ti iru ẹniti nrìn sibẹ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 22 Oluwa wipe, emi o tun mu pada lati Baṣani wá, emi o tun mu wọn pada lati ibu okun wá. 23 Ki ẹsẹ rẹ ki o le pọ́n ninu ẹ̀jẹ awọn ọta rẹ, ati àhọn awọn aja rẹ ninu rẹ̀ na. 24 Nwọn ti ri ìrin rẹ, Ọlọrun; ani ìrin Ọlọrun mi, Ọba mi, ninu ibi mimọ́ nì. 25 Awọn akọrin lọ niwaju, awọn olohun-elo orin kẹhin; larin awọn ọmọbinrin ti nwọn nlu ìlu. 26 Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun li ẹgbẹgbẹ, ani fun Oluwa, ẹnyin ti o ti orisun Israeli wá. 27 Nibẹ ni Benjamini kekere wà, pẹlu olori wọn, awọn ọmọ-alade Juda pẹlu awọn igbimọ wọn, awọn ọmọ-alade Sebuloni, ati awọn ọmọ-alade Naftali. 28 Ọlọrun rẹ ti paṣẹ agbara rẹ: Ọlọrun fi ẹsẹ eyi ti o ti ṣe fun wa mulẹ. 29 Nitori tempili rẹ ni Jerusalemu li awọn ọba yio ma mu ọrẹ fun ọ wá. 30 Ba awọn ẹranko ẽsu wi, ọ̀pọlọpọ awọn akọ-malu, pẹlu awọn ọmọ-malu enia, titi olukulùku yio fi foribalẹ pẹlu ìwọn fadaka: tú awọn enia ti nṣe inu didùn si ogun ka. 31 Awọn ọmọ-alade yio ti Egipti jade wá; nisisiyi ni Etiopia yio nà ọwọ rẹ̀ si Ọlọrun. 32 Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹnyin ijọba aiye; ẹ kọrin iyìn si Oluwa. 33 Si ẹniti ngùn ati ọrun de ọrun atijọ; wò o, o fọhùn rẹ̀, eyi na li ohùn nla. 34 Ẹ jẹwọ agbara fun Ọlọrun; ọlá-nla rẹ̀ wà lori Israeli, ati agbara rẹ̀ mbẹ li awọsanma. 35 Ọlọrun, iwọ li ẹ̀ru lati ibi mimọ́ rẹ wọnni wá: Ọlọrun Israeli li On, ti nfi ilera ati agbara fun awọn enia rẹ̀. Olubukún li Ọlọrun!

Psalmu 69

Igbe fún Ìrànlọ́wọ́

1 ỌLỌRUN, gbà mi; nitoriti omi wọnni wọ̀ inu lọ si ọkàn mi. 2 Emi rì ninu irà jijin, nibiti ibuduro kò si, emi de inu omi jijin wọnni, nibiti iṣan-omi ṣàn bò mi lori. 3 Agara ẹkun mi da mi: ọfun mi gbẹ: oju kún mi nigbati emi duro de Ọlọrun mi. 4 Awọn ti o korira mi lainidi jù irun ori mi lọ: awọn ti nṣe ọta mi laiṣẹ, ti iba pa mi run, nwọn lagbara: nigbana ni mo san ohun ti emi kò mu. 5 Ọlọrun, iwọ mọ̀ wère mi, ẹ̀ṣẹ mi kò si lumọ kuro loju rẹ. 6 Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, máṣe jẹ ki oju ki o tì awọn ti o duro de ọ nitori mi: máṣe jẹ ki awọn ti nwá ọ ki o damu nitori mi, Ọlọrun Israeli. 7 Nitoripe nitori tirẹ li emi ṣe nrù ẹ̀gan; itiju ti bo mi loju. 8 Emi di àjeji si awọn arakunrin mi, ati alejo si awọn ọmọ iya mi. 9 Nitori ti itara ile rẹ ti jẹ mi tan; ati ẹ̀gan awọn ti o gàn ọ, ṣubu lù mi. 10 Nigbati mo sọkun, ti mo si nfi àwẹ jẹ ara mi ni ìya, eyi na si di ẹ̀gan mi. 11 Emi fi aṣọ ọ̀fọ sẹ aṣọ mi pẹlu: mo si di ẹni-owe fun wọn. 12 Awọn ti o joko li ẹnu-bode nsọ̀rọ si mi; emi si di orin awọn ọmuti. 13 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ. 14 Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni. 15 Máṣe jẹ ki kikún-omi ki o bò mi mọlẹ, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki ọgbun ki o gbé mi mì, ki o má si ṣe jẹ ki iho ki o pa ẹnu rẹ̀ de mọ́ mi. 16 Oluwa, da mi lohùn; nitori ti iṣeun ifẹ rẹ dara, yipada si mi gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ irọnu ãnu rẹ. 17 Ki o má si ṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara iranṣẹ rẹ: emi sa wà ninu ipọnju; yara, da mi lohùn. 18 Sunmọ ọkàn mi, si rà a pada: gbà mi nitori awọn ọta mi. 19 Iwọ ti mọ̀ ẹ̀gan mi ati ìtiju mi, ati alailọla mi: gbogbo awọn ọta mi li o wà niwaju rẹ. 20 Ẹgan ti bà mi ni inu jẹ; emi si kún fun ikãnu: emi si woye fun ẹniti yio ṣãnu fun mi, ṣugbọn kò si; ati fun awọn olutunu, emi kò si ri ẹnikan. 21 Nwọn fi orõro fun mi pẹlu li ohun jijẹ mi; ati li ongbẹ mi nwọn fun mi li ọti kikan ni mimu. 22 Jẹ ki tabili wọn ki o di ikẹkun niwaju wọn: fun awọn ti o wà li alafia, ki o si di okùn didẹ. 23 Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo. 24 Dà irunu rẹ si wọn lori, si jẹ ki ikannu ibinu rẹ ki o le wọn ba. 25 Jẹ ki ibujoko wọn ki o di ahoro; ki ẹnikẹni ki o máṣe gbe inu agọ wọn. 26 Nitori ti nwọn nṣe inunibini si ẹniti iwọ ti lù; nwọn si nsọ̀rọ ibinujẹ ti awọn ti iwọ ti ṣá li ọgbẹ. 27 Fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ wọn: ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o wá sinu ododo rẹ. 28 Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo. 29 Ṣugbọn talaka ati ẹni-ikãnu li emi, Ọlọrun jẹ ki igbala rẹ ki o gbé mi leke. 30 Emi o fi orin yìn orukọ Ọlọrun, emi o si fi ọpẹ gbé orukọ rẹ̀ ga. 31 Eyi pẹlu ni yio wù Oluwa jù ọda-malu tabi akọ-malu lọ ti o ni iwo ati bàta ẹsẹ. 32 Awọn onirẹlẹ yio ri eyi, inu wọn o si dùn: ọkàn ẹnyin ti nwá Ọlọrun yio si wà lãye. 33 Nitoriti Oluwa gbohùn awọn talaka, kò si fi oju pa awọn ara tubu rẹ̀ rẹ́. 34 Jẹ ki ọrun on aiye ki o yìn i, okun ati ohun gbogbo ti nrakò ninu wọn. 35 Nitoriti Ọlọrun yio gbà Sioni là, yio si kọ́ ilu Juda wọnni: ki nwọn ki o le ma gbe ibẹ, ki nwọn ki o le ma ni i ni ilẹ-ini. 36 Iru-ọmọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ni yio ma jogun rẹ̀: awọn ti o si fẹ orukọ rẹ̀ ni yio ma gbe inu rẹ̀.

Psalmu 70

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 ỌLỌRUN, yara gbà mi; Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ. 2 Ki oju ki o tì awọn ti nwá ọkàn mi, ki nwọn ki o si dãmu: ki nwọn ki o si pada sẹhin, ki a si dãmu awọn ti nwá ifarapa mi. 3 Ki a pa wọn li ẹhìn dà fun ère itiju awọn ti nwi pe, A! a! 4 Ki gbogbo awọn ti nwá ọ ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn nipa tirẹ: ki iru awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Ki a gbé Ọlọrun ga! 5 Ṣugbọn talaka ati alaini li emi: Ọlọrun, yara si mi: iwọ li oluranlọwọ ati olugbala mi: Oluwa, máṣe pẹ́ titi.

Psalmu 71

Adura Àgbàlagbà kan

1 OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: lai máṣe jẹ ki a dãmu mi. 2 Gbà mi nipa ododo rẹ, ki o si mu mi yọ̀: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbà mi. 3 Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi. 4 Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin. 5 Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi. 6 Ọwọ rẹ li a ti fi gbé mi duro lati inu wá: iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu iya mi wá: nipasẹ rẹ ni iyìn mi wà nigbagbogbo. 7 Emi dabi ẹni-iyanu fun ọ̀pọlọpọ enia, ṣugbọn iwọ li àbo mi ti o lagbara. 8 Jẹ ki ẹnu mi ki o kún fun iyìn rẹ ati fun ọlá rẹ li ọjọ gbogbo. 9 Máṣe ṣa mi ti ni ìgba ogbó; máṣe kọ̀ mi silẹ nigbati agbara mi ba yẹ̀. 10 Nitori awọn ọta mi nsọ̀rọ si mi; awọn ti nṣọ ọkàn mi si gbimọ̀ pọ̀. 11 Nwọn wipe, Ọlọrun ti kọ̀ ọ silẹ: ẹ lepa ki ẹ si mu u; nitori ti kò si ẹniti yio gbà a. 12 Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi. 13 Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi. 14 Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ. 15 Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀. 16 Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan. 17 Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ. 18 Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin. 19 Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ! 20 Iwọ ti o fi iṣẹ nla ati kikan hàn mi, ni yio si tun mi ji, yio si tun mu mi sọ si òke lati ọgbun ilẹ wá. 21 Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo. 22 Emi o si fi ohun-elo orin yìn ọ pẹlu, ani otitọ rẹ, Ọlọrun mi: iwọ li emi o ma fi duru kọrin si, iwọ Ẹni-Mimọ́ Israeli. 23 Ete mi yio yọ̀ gidigidi, nigbati mo ba nkọrin si ọ: ati ọkàn mi, ti iwọ ti rapada. 24 Ahọn mi pẹlu yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ titi li ọjọ gbogbo: nitoriti nwọn dãmu, a si doju ti awọn tí nwá ifarapa mi.

Psalmu 72

Adura Ọba

1 ỌLỌRUN, fi idajọ rẹ fun ọba, ati ododo rẹ fun ọmọ ọba. 2 On o ma fi ododo ṣe idajọ awọn enia rẹ, yio si ma fi ẹtọ́ ṣe idajọ awọn talaka rẹ. 3 Awọn òke nla yio ma mu alafia fun awọn enia wá, ati awọn òke kekeke nipa ododo. 4 On o ma ṣe idajọ awọn talaka enia, yio ma gbà awọn ọmọ awọn alaini, yio si fà aninilara ya pẹrẹ-pẹrẹ. 5 Nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ, niwọ̀n bi õrùn ati oṣupa yio ti pẹ to, lati irandiran. 6 On o rọ̀ si ilẹ bi ojò si ori koriko itẹ̀mọlẹ: bi ọwọ òjo ti o rin ilẹ. 7 Li ọjọ rẹ̀ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọ̀pọlopọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to. 8 On o si jọba lati okun de okun, ati lati odò nì de opin aiye. 9 Awọn ti o joko li aginju yio tẹriba fun u; awọn ọta rẹ̀ yio si lá erupẹ ilẹ. 10 Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá. 11 Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i. 12 Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ. 13 On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là. 14 On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀. 15 On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i. 16 Ikúnwọ ọkà ni yio ma wà lori ilẹ, lori awọn òke nla li eso rẹ̀ yio ma mì bi Lebanoni: ati awọn ti inu ilu yio si ma gbà bi koriko ilẹ. 17 Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun. 18 Olubukún li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun Israeli, ẹnikanṣoṣo ti nṣe ohun iyanu. 19 Olubukún li orukọ rẹ̀ ti o li ogo titi lai: ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rẹ̀; Amin Amin. 20 Adura Dafidi ọmọ Jesse pari.

Psalmu 73

IWE KẸTA

Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun

1 NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́. 2 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan. 3 Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu. 4 Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀. 5 Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran. 6 Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ. 7 Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ. 8 Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga. 9 Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já. 10 Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn. 11 Nwọn si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? ìmọ ha wà ninu Ọga-ogo? 12 Kiyesi i, awọn wọnyi li alaìwa-bi-ọlọrun, ẹniti aiye nsan, nwọn npọ̀ li ọrọ̀. 13 Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ. 14 Nitoripe ni gbogbo ọjọ li a nyọ mi lẹnu, a si nnà mi li orowurọ. 15 Bi emi ba pe, emi o fọ̀ bayi: kiyesi i, emi o ṣẹ̀ si iran awọn ọmọ rẹ. 16 Nigbati mo rò lati mọ̀ eyi, o ṣoro li oju mi. 17 Titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ́ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ̀ igbẹhin wọn. 18 Nitõtọ iwọ gbé wọn ka ibi yiyọ́: iwọ tì wọn ṣubu sinu iparun. 19 Bawo li a ti mu wọn lọ sinu idahoro yi, bi ẹnipe ni iṣẹju kan! ibẹru li a fi nrun wọn patapata. 20 Bi igbati ẹnikan ba ji li oju alá; bẹ̃ni Oluwa, nigbati iwọ ba ji, iwọ o ṣe àbuku àworan wọn. 21 Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi. 22 Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ. 23 Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu. 24 Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo. 25 Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ. 26 Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai. 27 Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ. 28 Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.

Psalmu 74

Ranti Wa, OLUWA

1 ỌLỌRUN, ẽṣe ti iwọ fi ta wa nù titi lai! ẽṣe ti ibinu rẹ fi nrú si agutan papa rẹ? 2 Ranti ijọ enia rẹ ti iwọ ti rà nigba atijọ; ilẹ-ini rẹ ti iwọ ti rà pada; òke Sioni yi, ninu eyi ti iwọ ngbe. 3 Gbé ẹsẹ rẹ soke si ahoro lailai nì; ani si gbogbo eyiti ọta ti fi buburu ṣe ni ibi-mimọ́. 4 Awọn ọta rẹ nke ramu-ramu lãrin ijọ enia rẹ; nwọn gbé asia wọn soke fun àmi. 5 Nwọn dabi ọkunrin ti ngbé akeke rẹ̀ soke ninu igbo didi, 6 Ṣugbọn nisisiyi iṣẹ ọnà finfin ni nwọn fi akeke ati òlu wó lulẹ pọ̀ li ẹ̃kan. 7 Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri. 8 Nwọn wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a run wọn pọ̀: nwọn ti kun gbogbo ile Ọlọrun ni ilẹ na. 9 Awa kò ri àmi wa: kò si woli kan mọ́: bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi yio ti pẹ to. 10 Ọlọrun, ọta yio ti kẹgan pẹ to? ki ọta ki o ha ma sọ̀rọ òdi si orukọ rẹ lailai? 11 Ẽṣe ti iwọ fi fa ọwọ rẹ sẹhin, ani ọwọ ọtún rẹ? fà a yọ jade kuro li õkan aiya rẹ ki o si pa a run. 12 Nitori Ọlọrun li Ọba mi li atijọ wá, ti nṣiṣẹ igbala lãrin aiye. 13 Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi. 14 Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù. 15 Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla. 16 Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun. 17 Iwọ li o ti pàla eti aiye: iwọ li o ṣe igba ẹ̀run ati igba otutu. 18 Ranti eyi, Oluwa, pe ọta nkẹgàn, ati pe awọn enia buburu nsọ̀rọ odi si orukọ rẹ. 19 Máṣe fi ọkàn àdaba rẹ le ẹranko igbẹ lọwọ: máṣe gbagbe ijọ awọn talaka rẹ lailai. 20 Juba majẹmu nì: nitori ibi òkunkun aiye wọnni o kún fun ibugbe ìka. 21 Máṣe jẹ ki ẹniti a ni lara ki o pada ni ìtiju; jẹ ki talaka ati alaini ki o yìn orukọ rẹ. 22 Ọlọrun, dide, gbà ẹjọ ara rẹ rò: ranti bi aṣiwere enia ti ngàn ọ lojojumọ. 23 Máṣe gbagbe ohùn awọn ọta rẹ: irọkẹ̀kẹ awọn ti o dide si ọ npọ̀ si i nigbagbogbo.

Psalmu 75

Ọlọrun Onídàájọ́

1 ỌLỌRUN, iwọ li awa fi ọpẹ fun, iwọ li awa fi ọpẹ fun nitori orukọ rẹ sunmọ itosi, iṣẹ iyanu rẹ fi hàn. 2 Nigbati akokò mi ba de, emi o fi otitọ ṣe idajọ. 3 Aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀ warìri: emi li o rù ọwọ̀n rẹ̀. 4 Emi wi fun awọn agberaga pe, Ẹ máṣe gbéraga mọ́: ati fun awọn enia buburu pe, Ẹ máṣe gbé iwo nì soke. 5 Ẹ máṣe gbé iwo nyin ga: ẹ máṣe fi ọrùn lile sọ̀rọ. 6 Nitori ti igbega kò ti ìla-õrùn wá, tabi ni ìwọ-õrùn, bẹ̃ni kì iṣe lati gusu wá. 7 Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke. 8 Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu. 9 Ṣugbọn emi o ma sọ titi lai, emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun Jakobu. 10 Gbogbo iwo awọn enia buburu li emi o ke kuro; ṣugbọn iwo awọn olododo li emi o gbé soke.

Psalmu 76

Ọlọrun Ajàṣẹ́gun

1 NI Juda li a gbe mọ̀ Ọlọrun: orukọ rẹ̀ si pọ̀ ni Israeli. 2 Ni Salemu pẹlu li agọ rẹ̀ wà, ati ibujoko rẹ̀ ni Sioni. 3 Nibẹ li o gbe ṣẹ́ ọfà, ọrun, apata, ati idà, ati ogun na. 4 Iwọ li ogo ati ọlá jù òke-nla ikogun wọnni lọ. 5 A kó awọn alaiya lile ni ikogun, nwọn ti sùn orun wọn, gbogbo ọkunrin alagbara kò si ri ọwọ wọn. 6 Nipa ibawi rẹ, Ọlọrun Jakobu, ati kẹkẹ́-ogun ati ẹṣin sun orun asunkú. 7 Iwọ, ani iwọ li o ni ìbẹru: ati tani yio le duro niwaju rẹ, nigbati iwọ ba binu lẹ̃kan? 8 Iwọ mu idajọ di gbigbọ́ lati ọrun wá: ilẹ aiye bẹ̀ru o si duro jẹ. 9 Nigbati Ọlọrun dide si idajọ, lati gbà gbogbo ọlọkan-tutu aiye là. 10 Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure. 11 Ẹ ṣe ileri ifẹ, ki ẹ si san a fun Oluwa, Ọlọrun nyin: jẹ ki gbogbo awọn ti o yi i ka ki o mu ẹ̀bun wá fun ẹniti a ba ma bẹ̀ru. 12 On o ke ẹmi awọn ọmọ alade kuro: on si di ẹ̀ru si awọn ọba aiye.

Psalmu 77

Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú

1 EMI fi ohùn mi kigbe si Ọlọrun, ani si Ọlọrun ni mo fi ohùn mi kepè; o si fi eti si mi. 2 Li ọjọ ipọnju mi emi ṣe afẹri Ọlọrun: ọwọ mi nnà li oru, kò si rẹ̀ silẹ: ọkàn mi kọ̀ ati tù ninu. 3 Emi ranti Ọlọrun, emi kẹdun: emi ṣe aroye, ẹmi mi si rẹ̀wẹsi. 4 Iwọ kò fẹ ki emi ki o fi oju ba orun: ẹnu yọ mi tobẹ̃ ti emi kò le sọ̀rọ. 5 Emi ti nrò ọjọ atijọ, ọdun igbani. 6 Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ. 7 Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́? 8 Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai? 9 Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́? 10 Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo! 11 Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ. 12 Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ. 13 Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun? 14 Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia. 15 Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu. 16 Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ. 17 Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu. 18 Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì. 19 Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀. 20 Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.

Psalmu 78

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 FI eti silẹ, ẹnyin enia mi, si ofin mi: dẹ eti nyin silẹ si ọ̀rọ ẹnu mi. 2 Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade. 3 Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa. 4 Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ. 5 Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn. 6 Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn: 7 Ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rẹ̀ mọ́. 8 Ki nwọn ki o máṣe dabi awọn baba wọn, iran alagidi ati ọlọ̀tẹ̀; iran ti kò fi ọkàn wọn le otitọ, ati ẹmi ẹniti kò ba Ọlọrun duro ṣinṣin. 9 Awọn ọmọ Efraimu ti o hamọra ogun, ti nwọn mu ọrun, nwọn yipada li ọjọ ogun. 10 Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, nwọn si kọ̀ lati ma rìn ninu ofin rẹ̀. 11 Nwọn si gbagbe iṣẹ rẹ̀, ati ohun iyanu rẹ̀, ti o ti fi hàn fun wọn. 12 Ohun iyanu ti o ṣe niwaju awọn baba wọn ni ilẹ Egipti, ani ni igbẹ Soani. 13 O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe. 14 Li ọsan pẹlu o fi awọsanma ṣe amọna wọn, ati li oru gbogbo pẹlu imọlẹ iná. 15 O sán apata li aginju, o si fun wọn li omi mímu lọpọlọpọ bi ẹnipe lati inu ibú wá. 16 O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla. 17 Nwọn si tún ṣẹ̀ si i; ni ṣiṣọtẹ si Ọga-ogo li aginju. 18 Nwọn si dán Ọlọrun wò li ọkàn wọn, ni bibère onjẹ fun ifẹkufẹ wọn. 19 Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju? 20 Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀? 21 Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli; 22 Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀. 23 O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ. 24 O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun. 25 Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo. 26 O mu afẹfẹ ìla-õrun fẹ li ọrun, ati nipa agbara rẹ̀ o mu afẹfẹ gusu wá. 27 O rọ̀jo ẹran si wọn pẹlu bi erupẹ ilẹ, ati ẹiyẹ abiyẹ bi iyanrin okun. 28 O si jẹ ki o bọ́ si ãrin ibudo wọn, yi agọ wọn ka. 29 Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn. 30 Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn. 31 Ibinu Ọlọrun de si ori wọn, o pa awọn ti o sanra ninu wọn, o si lù awọn ọdọmọkunrin Israeli bolẹ. 32 Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́. 33 Nitorina li o ṣe run ọjọ wọn li asan, ati ọdun wọn ni ijaiya. 34 Nigbati o pa wọn, nigbana ni nwọn wá a kiri: nwọn si pada, nwọn bère Ọlọrun lakokò, 35 Nwọn si ranti pe, Ọlọrun li apata wọn, ati Ọlọrun Ọga-ogo li Oludande wọn, 36 Ṣugbọn ẹnu wọn ni nwọn fi pọ́n ọ, nwọn si fi ahọn wọn ṣeke si i. 37 Nitori ọkàn wọn kò ṣe dẽde pẹlu rẹ̀, bẹ̃ni nwọn kò si duro ṣinṣin ni majẹmu rẹ̀. 38 Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke. 39 Nitoriti o ranti pe, enia ṣa ni nwọn; afẹfẹ ti nkọja lọ, ti kò si tun pada wá mọ. 40 Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ! 41 Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli. 42 Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta. 43 Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani. 44 Ti o si sọ odò wọn di ẹ̀jẹ; ati omi ṣiṣan wọn, ti nwọn kò fi le mu u. 45 O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn. 46 O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú. 47 O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn. 48 O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana. 49 O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn. 50 O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun. 51 O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu: 52 Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran. 53 O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ. 54 O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà. 55 O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn. 56 Ṣugbọn nwọn dan a wò, nwọn si ṣọ̀tẹ si Ọlọrun Ọga-ogo, nwọn kò si pa ẹri rẹ̀ mọ́. 57 Ṣugbọn nwọn yipada, nwọn ṣe alaiṣotitọ bi awọn baba wọn: nwọn si pẹhinda si apakan bi ọrun ẹ̀tan. 58 Nitori ti nwọn fi ibi giga wọn bi i ninu, nwọn si fi ere finfin wọn mu u jowu. 59 Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi. 60 Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia. 61 O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì. 62 O fi awọn enia rẹ̀ fun idà pẹlu; o si binu si ilẹ-ini rẹ̀. 63 Iná run awọn ọdọmọkunrin wọn; a kò si fi orin sin awọn wundia wọn ni iyawo. 64 Awọn alufa wọn ti oju idà ṣubu; awọn opó wọn kò si pohunrere ẹkún. 65 Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini. 66 O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye. 67 Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu: 68 Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ. 69 O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai. 70 O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá: 71 Lati má tọ̀ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ́ Jakobu, enia rẹ̀, ati Israeli, ilẹ-ini rẹ̀. 72 Bẹ̃li o bọ́ wọn gẹgẹ bi ìwa-titọ inu rẹ̀; o si fi ọgbọ́n ọwọ rẹ̀ ṣe amọna wọn.

Psalmu 79

Adura Ìdáǹdè Orílẹ̀-Èdè

1 ỌLỌRUN, awọn keferi wá si ilẹ-ini rẹ; tempili mimọ́ rẹ ni nwọn sọ di ẽri; nwọn sọ Jerusalemu di òkiti-alapa. 2 Okú awọn iranṣẹ rẹ ni nwọn fi fun ẹiyẹ oju-ọrun li onjẹ, ẹran-ara awọn enia mimọ́ rẹ fun ẹranko ilẹ. 3 Ẹ̀jẹ wọn ni nwọn ta silẹ bi omi yi Jerusalemu ka; kò si si ẹniti yio gbé wọn sìn. 4 Awa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣuti si awọn ti o yi wa ka. 5 Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o binu titi lailai? owú rẹ yio ha ma jó bi iná? 6 Dà ibinu rẹ si ori awọn keferi ti kò mọ̀ ọ, ati si ori awọn ijọba ti kò kepè orukọ rẹ. 7 Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro. 8 Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi. 9 Ràn wa lọwọ, Ọlọrun igbala wa, nitori ogo orukọ rẹ: ki o si gbà wa, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ wa nù, nitori orukọ rẹ. 10 Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà? jẹ ki a mọ̀ igbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ ti a ta silẹ loju wa ninu awọn keferi. 11 Jẹ ki imi-ẹdun onde nì ki o wá siwaju rẹ: gẹgẹ bi titobi agbara rẹ, iwọ dá awọn ti a yàn si pipa silẹ: 12 Ki o si san ẹ̀gan wọn nigba meje fun awọn aladugbo wa li aiya wọn, nipa eyiti nwọn ngàn ọ, Oluwa. 13 Bẹ̃li awa enia rẹ ati agutan papa rẹ, yio ma fi ọpẹ fun ọ lailai, awa o ma fi iyìn rẹ hàn lati irandiran.

Psalmu 80

Fi Ojurere Wò Wá

1 FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade. 2 Niwaju Efraimu ati Benjamini ati Manasse rú ipa rẹ soke ki o si wá fun igbala wa. 3 Tún wa yipada, Ọlọrun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là. 4 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, iwọ o ti binu pẹ to si adura awọn enia rẹ? 5 Iwọ fi onjẹ omije bọ́ wọn; iwọ si fun wọn li omije mu li ọ̀pọlọpọ. 6 Iwọ sọ wa di ijà fun awọn aladugbo wa: awọn ọta wa si nrẹrin ninu ara wọn. 7 Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là. 8 Iwọ ti mu ajara kan jade ti Egipti wá: iwọ ti tì awọn keferi jade, iwọ si gbin i. 9 Iwọ ṣe àye silẹ fun u, iwọ si mu u ta gbòngbo jinlẹ̀, o si kún ilẹ na. 10 A fi ojiji rẹ̀ bò awọn òke mọlẹ, ati ẹka rẹ̀ dabi igi kedari Ọlọrun. 11 O yọ ẹka rẹ̀ sinu okun, ati ọwọ rẹ̀ si odò nla nì. 12 Ẽṣe ti iwọ ha fi ya ọgbà rẹ̀ bẹ̃, ti gbogbo awọn ẹniti nkọja lọ li ọ̀na nká a? 13 Imado lati inu igbo wá mba a jẹ, ati ẹranko igbẹ njẹ ẹ run. 14 Yipada, awa mbẹ ọ, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: wolẹ lati ọrun wá, ki o si wò o, ki o si bẹ àjara yi wò: 15 Ati agbala-àjara ti ọwọ ọtún rẹ ti gbin, ati ọmọ ti iwọ ti mule fun ara rẹ. 16 O jona, a ke e lulẹ: nwọn ṣegbe nipa ibawi oju rẹ. 17 Jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà lara ọkunrin ọwọ ọtún rẹ nì, lara ọmọ-enia ti iwọ ti mule fun ara rẹ. 18 Bẹ̃li awa kì yio pada sẹhin kuro lọdọ rẹ: mu wa yè, awa o si ma pè orukọ rẹ. 19 Tún wa yipada, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.

Psalmu 81

Orin fún Àkókò Àsè

1 KỌRIN soke si Ọlọrun, ipa wa: ẹ ho iho ayọ̀ si Ọlọrun Jakobu. 2 Ẹ mu orin mimọ́, ki ẹ si mu ìlu wa, duru didùn pẹlu ohun-elo orin mimọ́. 3 Ẹ fun ipè li oṣù titún, ni ìgbà ti a lana silẹ, li ọjọ ajọ wa ti o ni ironu. 4 Nitori eyi li aṣẹ fun Israeli, ati ofin Ọlọrun Jakobu. 5 Eyi li o dasilẹ ni ẹrí fun Josefu, nigbati o là ilẹ Egipti ja; nibiti mo gbe gbọ́ ede ti kò ye mi. 6 Mo gbé ejika rẹ̀ kuro ninu ẹrù: mo si gbà agbọn li ọwọ rẹ̀. 7 Iwọ pè ninu ipọnju, emi si gbà ọ; emi da ọ lohùn nibi ìkọkọ ãra: emi ridi rẹ nibi omi ija. 8 Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi. 9 Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji. 10 Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u. 11 Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi. 12 Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn. 13 Ibaṣepe awọn enia mi ti gbọ́ ti emi, ati ki Israeli ki o ma rìn nipa ọ̀na mi! 14 Emi iba ti ṣẹ́ awọn ọta wọn lọgan, emi iba si ti yi ọwọ mi pada si awọn ọta wọn. 15 Awọn akorira Oluwa iba ti fi ori wọn balẹ fun u; igba wọn iba si duro pẹ titi. 16 Alikama daradara ni on iba ma fi bọ́ wọn pẹlu: ati oyin inu apata ni emi iba si ma fi tẹ́ ọ lọrun.

Psalmu 82

Ọlọrun, Ọba Àwọn Ọba

1 ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara; o nṣe idajọ ninu awọn ọlọrun. 2 Ẹnyin o ti ṣe idajọ aiṣõtọ pẹ to, ti ẹ o si ma ṣe ojuṣaju awọn enia buburu? 3 Ṣe idajọ talaka, ati ti alaini-baba: ṣe otitọ si awọn olupọnju ati alaini. 4 Gbà talaka ati alaini: yọ wọn li ọwọ awọn enia buburu. 5 Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn. 6 Emi ti wipe, ọlọrun li ẹnyin; awọn ọmọ Ọga-ogo si ni gbogbo nyin. 7 Ṣugbọn ẹnyin o kú bi enia, ẹnyin o si ṣubu bi ọkan ninu awọn ọmọ-alade. 8 Ọlọrun, dide, ṣe idajọ aiye: nitori iwọ ni yio ni orilẹ-ède gbogbo.

Psalmu 83

Adura Ìṣẹ́gun

1 MAṢE dakẹ, Ọlọrun: máṣe pa ẹnu rẹ mọ́, ki o má si ṣe duro jẹ, Ọlọrun. 2 Sa wò o, awọn ọta rẹ nrọkẹ̀kẹ: awọn ti o korira rẹ ti gbé ori soke. 3 Nwọn ti gbimọ̀ arekereke si awọn enia rẹ, nwọn si ti gbèro si awọn ẹni-ìkọ̀kọ̀ rẹ. 4 Nwọn ti wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a ke wọn kuro lati má wà li orilẹ-ède; ki orukọ Israeli ki o máṣe si ni iranti mọ́. 5 Nitoriti nwọn ti gbimọ̀ pọ̀ ṣọkan: nwọn ti dimọlu si ọ. 6 Agọ Edomu, ati ti awọn ọmọ Iṣmaeli; ti Moabu, ati awọn ọmọ Hagari. 7 Gebali, ati Ammoni, ati Amaleki: awọn ara Filistia pẹlu awọn ara Tire; 8 Assuri pẹlu dapọ̀ mọ wọn: nwọn ràn awọn ọmọ Lotu lọwọ. 9 Ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani; bi Sisera, bi Jabini, li odò Kiṣoni. 10 Ẹniti o ṣegbe ni Endori: nwọn di àtan fun ilẹ. 11 Ṣe awọn ọlọla wọn bi Orebu ati bi Sebu: ani, gbogbo awọn ọmọ-alade wọn bi Seba ati Salmuna. 12 Awọn ti o wipe, Ẹ jẹ ki a gbà ibugbe Ọlọrun wọnni fun ara wa ni ini. 13 Ọlọrun mi, ṣe wọn bi ãjà; bi akeku koriko niwaju afẹfẹ. 14 Bi iná ti ijo igbo, ati bi ọwọ́ iná ti imu òke-nla gbiná; 15 Bẹ̃ni ki o fi ẹ̀fufu rẹ ṣe inunibini si wọn, ki o si fi ìji rẹ dẹrubà wọn. 16 Fi ìtiju kún wọn li oju: ki nwọn o le ma ṣe afẹri orukọ rẹ, Oluwa. 17 Ki nwọn ki o dãmu ki a si pọ́n wọn loju lailai; nitõtọ, ki a dojutì wọn, ki nwọn ki o ṣegbé. 18 Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.

Psalmu 84

Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun

1 AGỌ rẹ wọnni ti li ẹwà to, Oluwa awọn ọmọ-ogun! 2 Ọkàn mi nfà nitõtọ, o tilẹ pe ongbẹ fun agbala Oluwa: aiya mi ati ara mi nkigbe si Ọlọrun alãye. 3 Nitõtọ, ologoṣẹ ri ile, ati alapandẹdẹ tẹ́ itẹ fun ara rẹ̀, nibiti yio gbe ma pa awọn ọmọ rẹ̀ mọ́ si, ani ni pẹpẹ rẹ wọnni, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọba mi ati Ọlọrun mi. 4 Ibukún ni fun awọn ti ngbe inu ile rẹ: nwọn o ma yìn ọ sibẹ. 5 Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà. 6 Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o. 7 Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun. 8 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, gbọ́ adura mi; fi eti si i, Ọlọrun Jakobu. 9 Kiyesi i, Ọlọrun asà wa, ki o si ṣiju wò oju Ẹni-ororo rẹ. 10 Nitori pe ọjọ kan ninu agbala rẹ sanju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ ki nkuku ma ṣe adena ni ile Ọlọrun mi, jù lati ma gbe agọ ìwa-buburu. 11 Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede. 12 Oluwa awọn ọmọ-ogun, ibukún ni fun oluwarẹ̀ na ti o gbẹkẹle ọ.

Psalmu 85

Adura Ire Orílẹ̀-Èdè

1 OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀. 2 Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. 3 Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ. 4 Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá. 5 Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran? 6 Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ? 7 Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ. 8 Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were. 9 Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa. 10 Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu. 11 Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá. 12 Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá. 13 Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na.

Psalmu 86

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini. 2 Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ. 3 Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ. 4 Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. 5 Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ. 6 Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi. 7 Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn. 8 Oluwa, ninu awọn oriṣa kò si ọ̀kan ti o dabi rẹ, bẹ̃ni kò si iṣẹ kan ti o dabi iṣẹ rẹ. 9 Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ. 10 Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun. 11 Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ. 12 Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai. 13 Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin. 14 Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn. 15 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ. 16 Yipada si mi ki o si ṣãnu fun mi; fi ipá rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o si gbà ọmọkunrin iranṣẹ-birin rẹ là. 17 Fi àmi hàn mi fun rere; ki awọn ti o korira mi ki o le ri i, ki oju ki o le tì wọn, nitori iwọ, Oluwa, li o ti ràn mi lọwọ ti o si tù mi ninu.

Psalmu 87

Ìyìn Sioni

1 IPILẸ rẹ̀ mbẹ lori òke mimọ́ wọnni. 2 Oluwa fẹ ẹnu-ọ̀na Sioni jù gbogbo ibujoko Jakobu lọ. 3 Ohun ogo li a nsọ niti rẹ? Ilu Ọlọrun! 4 Emi o da orukọ Rahabu ati Babeli lãrin awọn ti o mọ̀ mi: kiyesi Filistia ati Tire, pẹlu Etiopia: a bi eleyi nibẹ. 5 Ati ni Sioni li a o wipe: ọkunrin yi ati ọkunrin nì li a bi ninu rẹ̀: ati Ọga-ogo tikararẹ̀ ni yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ. 6 Oluwa yio kà, nigbati o ba nkọ orukọ awọn enia, pe, a bi eleyi nibẹ. 7 Ati awọn olorin ati awọn ti nlu ohun-elo orin yio wipe: Gbogbo orisun mi mbẹ ninu rẹ.

Psalmu 88

Adura nígbà ìpọ́njú

1 OLUWA Ọlọrun igbala mi, emi nkigbe lọsan ati loru niwaju rẹ. 2 Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ: dẹ eti rẹ silẹ si igbe mi. 3 Nitori ti ọkàn mi kún fun ipọnju, ẹmi mi si sunmọ isa-okú. 4 A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá. 5 Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ. 6 Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun. 7 Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja. 8 Iwọ ti mu awọn ojulumọ mi jina si mi; iwọ si sọ mi di irira si wọn; a se mi mọ́, emi kò le jade. 9 Oju mi nkãnu nitori ipọnju: Oluwa, emi ti npè ọ lojojumọ, emi si ti nawọ mi si ọ. 10 Iwọ o fi iṣẹ iyanu rẹ hàn fun okú bi? awọn okú yio ha dide ki nwọn si ma yìn ọ bi? 11 A o ha fi iṣeun ifẹ rẹ hàn ni isà-òkú bi? tabi otitọ rẹ ninu iparun? 12 A ha le mọ̀ iṣẹ iyanu rẹ li okunkun bi? ati ododo rẹ ni ilẹ igbagbe? 13 Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ. 14 Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi? 15 Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère. 16 Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro. 17 Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan. 18 Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun.

Psalmu 89

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi

1 EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran. 2 Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun. 3 Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi, 4 Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran, 5 Ọrun yio si ma yìn iṣẹ-iyanu rẹ, Oluwa, otitọ rẹ pẹlu ninu ijọ enia mimọ́ rẹ. 6 Nitori pe, tali o wà li ọrun ti a le fi wé Oluwa? tani ninu awọn ọmọ alagbara, ti a le fi wé Oluwa? 7 Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká. 8 Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká. 9 Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ. 10 Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká. 11 Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn. 12 Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ. 13 Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ. 14 Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ. 15 Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ. 16 Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke. 17 Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke, 18 Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa. 19 Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia. 20 Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori: 21 Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le. 22 Ọtá kì yio bère lọdọ rẹ̀; bẹ̃ni awọn ọmọ iwà-buburu kì yio pọ́n ọ loju. 23 Emi o si lu awọn ọta rẹ̀ bolẹ niwaju rẹ̀, emi o si yọ awọn ti o korira rẹ̀ lẹnu. 24 Ṣugbọn otitọ mi ati ãnu mi yio wà pẹlu rẹ̀; ati li orukọ mi li a o gbé iwo rẹ̀ soke. 25 Emi o gbé ọwọ rẹ̀ le okun, ati ọwọ ọtún rẹ̀ le odò nla nì. 26 On o kigbe pè mi pe, Iwọ ni baba mi, Ọlọrun mi, ati apata igbala mi. 27 Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ. 28 Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin. 29 Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun. 30 Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba kọ̀ ofin mi silẹ, ti nwọn kò si rìn nipa idajọ mi; 31 Bi nwọn ba bá ilana mi jẹ, ti nwọn kò si pa ofin mi mọ́, 32 Nigbana li emi o fi ọgọ bẹ irekọja wọn wò, ati ẹ̀ṣẹ wọn pẹlu ìna. 33 Ṣugbọn iṣeun-ifẹ mi li emi kì yio gbà lọwọ rẹ̀, bẹ̃li emi kì yio jẹ ki otitọ mi ki o yẹ̀. 34 Majẹmu mi li emi kì yio dà, bẹ̃li emi kì yio yi ohun ti o ti ète mi jade pada. 35 Lẹrinkan ni mo ti fi ìwa-mimọ́ mi bura pe, emi kì yio purọ fun Dafidi. 36 Iru-ọmọ rẹ̀ yio duro titi lailai, ati itẹ́ rẹ̀ bi õrun niwaju mi. 37 A o fi idi rẹ̀ mulẹ lailai bi òṣupa, ati bi ẹlẹri otitọ li ọrun.

Ìlérí Ọlọrun fun Dafidi

38 Ṣugbọn iwọ ti ṣa tì, iwọ si korira, iwọ ti binu si Ẹni-ororo rẹ. 39 Iwọ ti sọ majẹmu iranṣẹ rẹ di ofo: iwọ ti sọ ade rẹ̀ si ilẹ. 40 Iwọ ti fa ọgba rẹ̀ gbogbo ya: iwọ ti mu ilu-olodi rẹ̀ di ahoro. 41 Gbogbo awọn ti nkọja lọ li ọ̀na nfi ṣe ijẹ: on si di ẹ̀gan fun awọn aladugbo rẹ̀. 42 Iwọ ti gbé ọwọ ọtún awọn ọta rẹ̀ soke; iwọ mu gbogbo awọn ọta rẹ̀ yọ̀. 43 Iwọ si ti yi oju idà rẹ̀ pada pẹlu, iwọ kò si mu u duro li oju ogun. 44 Iwọ ti mu ogo rẹ̀ tẹ́, iwọ si wọ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ-yilẹ. 45 Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o.

Adura ìdáǹdè

46 Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi? 47 Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan? 48 Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú. 49 Oluwa, nibo ni iṣeun-ifẹ rẹ atijọ wà, ti iwọ bura fun Dafidi ninu otitọ rẹ? 50 Oluwa, ranti ẹ̀gan awọn iranṣẹ rẹ, ti emi nrù li aiya mi lati ọdọ gbogbo ọ̀pọ enia. 51 Ti awọn ọta rẹ fi kẹgàn, Oluwa: ti nwọn fi ngàn ipasẹ Ẹni-ororo rẹ. 52 Olubukún ni Oluwa si i titi lailai. Amin ati Amin.

IWE IV

Psalmu 90

IWE KẸRIN

Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ

1 OLUWA, iwọ li o ti nṣe ibujoko wa lati irandiran. 2 Ki a to bí awọn òke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun. 3 Iwọ sọ enia di ibajẹ; iwọ si wipe, Ẹ pada wá, ẹnyin ọmọ enia. 4 Nitoripe igbati ẹgbẹrun ọdun ba kọja li oju rẹ, bi aná li o ri, ati bi igba iṣọ́ kan li oru. 5 Iwọ kó wọn lọ bi ẹnipe ni ṣiṣan-omi; nwọn dabi orun; ni kutukutu nwọn dabi koriko ti o dagba soke. 6 Ni Kutukutu o li àwọ lara, o si dàgba soke, li asalẹ a ké e lulẹ, o si rọ. 7 Nitori awa di egbé nipa ibinu rẹ, ati nipa ibinu rẹ ara kò rọ̀ wa. 8 Iwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ wa ka iwaju rẹ, ohun ìkọkọ wa mbẹ ninu imọlẹ iwaju rẹ. 9 Nitori ọjọ wa gbogbo nyipo lọ ninu ibinu rẹ: awa nlo ọjọ wa bi alá ti a nrọ́. 10 Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lãla on ibinujẹ ni; nitori pe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ. 11 Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ. 12 Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n. 13 Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ. 14 Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo. 15 Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu. 16 Jẹ ki iṣẹ rẹ ki o hàn si awọn ọmọ-ọ̀dọ rẹ, ati ogo rẹ si awọn ọmọ wọn. 17 Jẹ ki ẹwà Oluwa Ọlọrun wa ki o wà lara wa: ki iwọ ki o si fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ lara wa, bẹ̃ni iṣẹ ọwọ wa ni ki iwọ ki o fi idi rẹ̀ mulẹ.

Psalmu 91

Ọlọrun Aláàbò wa

1 ẸNITI o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo ni yio ma gbe abẹ ojiji Olodumare. 2 Emi o wi fun Ọlọrun pe, Iwọ li àbo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle. 3 Nitõtọ on o gbà ọ ninu ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ, ati ninu àjakalẹ-àrun buburu. 4 Yio fi iyẹ́ rẹ̀ bò ọ, abẹ iyẹ́-apa rẹ̀ ni iwọ o si gbẹkẹle: otitọ rẹ̀ ni yio ṣe asà ati apata rẹ. 5 Iwọ kì yio bẹ̀ru nitori ẹ̀ru oru; tabi fun ọfa ti nfo li ọsán; 6 Tabi fun àjakalẹ-àrun ti nrìn kiri li okunkun, tabi fun iparun ti nrun-ni li ọsángangan. 7 Ẹgbẹrun yio ṣubu li ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbarun li apa ọtún rẹ: ṣugbọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ. 8 Kiki oju rẹ ni iwọ o ma fi ri, ti o si ma fi wo ère awọn enia buburu. 9 Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ. 10 Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ. 11 Nitori ti yio fi aṣẹ fun awọn angeli rẹ̀ nitori rẹ, lati pa ọ mọ́ li ọ̀na rẹ gbogbo. 12 Nwọn o gbé ọ soke li ọwọ́ wọn, ki iwọ ki o má ba fi ẹṣẹ rẹ gbun okuta. 13 Iwọ o kọja lori kiniun ati pamọlẹ: ẹgbọrọ kiniun ati ejò-nla ni iwọ o fi ẹsẹ tẹ̀-mọlẹ. 14 Nitori ti o fẹ ifẹ rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ṣe gbà a: emi o gbé e leke, nitori ti o mọ̀ orukọ mi. 15 On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn: emi o pẹlu rẹ̀ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u. 16 Ẹmi gigun li emi o fi tẹ́ ẹ lọrun, emi o si fi igbala mi hàn a.

Psalmu 92

Orin Ìyìn

1 OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo: 2 Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ. 3 Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu. 4 Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ. 5 Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi. 6 Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia. 7 Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni: 8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa li ẹniti o ga titi lai. 9 Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka. 10 Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori. 11 Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi. 12 Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni. 13 Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa. 14 Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini; 15 Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.

Psalmu 93

Ọlọrun Ọba

1 OLUWA jọba, ọla-nla li o wọ li aṣọ; agbara ni Oluwa wọ̀ li aṣọ, o fi di ara rẹ̀ li amure: o si fi idi aiye mulẹ, ti kì yio fi le yi. 2 Lati igba atijọ li a ti fi idi itẹ́ rẹ kalẹ, ati aiye-raiye ni Iwọ. 3 Iṣan-omi gbé ohùn wọn soke, Oluwa, iṣan-omi gbé ohùn wọn soke; iṣan-omi gbé riru omi wọn soke. 4 Oluwa li ologo, o li ogo jù ariwo omi pupọ lọ, jù riru omi nla, ani jù agbara riru omi okun lọ. 5 Otitọ li ẹri rẹ: ìwa-mimọ́ li o yẹ ile rẹ lailai, Oluwa.

Psalmu 94

Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé

1 OLUWA, Ọlọrun ẹsan; Ọlọrun ẹsan, fi ara rẹ hàn. 2 Gbé ara rẹ soke, iwọ onidajọ aiye: san ẹsan fun awọn agberaga. 3 Oluwa, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu yio fi ma leri? 4 Nwọn o ti ma dà ọ̀rọ nù ti nwọn o ma sọ ohun lile pẹ to? ti gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio fi ma fi ara wọn leri. 5 Oluwa, nwọn fọ́ awọn enia rẹ tutu, nwọn si nyọ awọn enia-ini rẹ lẹnu. 6 Nwọn pa awọn opó ati alejo, nwọn si pa awọn ọmọ alaini-baba. 7 Sibẹ nwọn wipe, Oluwa kì yio ri i, bẹ̃li Ọlọrun Jakobu kì yio kà a si, 8 Ki oye ki o ye nyin, ẹnyin ope ninu awọn enia: ati ẹnyin aṣiwere, nigbawo li ẹnyin o gbọ́n? 9 Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ́ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran? 10 Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ. 11 Oluwa mọ̀ ìro-inu enia pe: asan ni nwọn. 12 Ibukún ni fun enia na ẹniti iwọ nà, Oluwa, ti iwọ si kọ́ lati inu ofin rẹ wá; 13 Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu. 14 Nitoripe Oluwa kì yio ṣa awọn enia rẹ̀ tì, bẹ̃ni kì yio kọ̀ awọn enia-ini rẹ̀ silẹ. 15 Ṣugbọn idajọ yio pada si ododo: gbogbo ọlọkàn diduro ni yio si ma tọ̀ ọ lẹhin. 16 Tani yio dide si awọn oluṣe buburu fun mi? tabi tani yio dide si awọn oniṣẹ ẹ̀ṣe fun mi? 17 Bikoṣe bi Oluwa ti ṣe oluranlọwọ mi; ọkàn mi fẹrẹ joko ni idakẹ. 18 Nigbati mo wipe, Ẹsẹ mi yọ́; Oluwa, ãnu rẹ dì mi mu. 19 Ninu ọ̀pọlọpọ ibinujẹ mi ninu mi, itunu rẹ li o nmu inu mi dùn. 20 Itẹ́ ẹ̀ṣẹ ha le ba ọ kẹgbẹ pọ̀, ti nfi ofin dimọ ìwa-ika? 21 Nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si ọkàn olododo, nwọn si da ẹ̀jẹ alaiṣẹ lẹbi. 22 Ṣugbọn Oluwa li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi, 23 On o si mu ẹ̀ṣẹ wọn bọ̀ sori ara wọn, yio si ke wọn kuro ninu ìwa-buburu wọn: Oluwa Ọlọrun wa, yio ke wọn kuro.

Psalmu 95

Orin Ìyìn

1 ẸWÁ, ẹ jẹ ki a kọrin si Oluwa: ẹ jẹ ki a hó iho ayọ̀ si apata igbala wa. 2 Ẹ jẹ ki a fi ọpẹ wá si iwaju rẹ̀, ki a si fi orin mimọ́ hó iho ayọ̀ si ọdọ rẹ̀. 3 Nitori Oluwa, Ọlọrun ti o tobi ni, ati Ọba ti o tobi jù gbogbo oriṣa lọ, 4 Ni ikawọ ẹniti ibi ọgbun ilẹ wà: giga awọn òke nla ni tirẹ̀ pẹlu. 5 Tirẹ̀ li okun, on li o si dá a: ọwọ rẹ̀ li o si dá iyangbẹ ilẹ. 6 Ẹ wá, ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹda wa. 7 Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀,

Ọlọrun Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ sọ̀rọ̀

8 Ẹ má sé aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju. 9 Nigbati awọn baba nyin dan mi wò, ti nwọn wadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi. 10 Ogoji-ọdun tọ̀tọ ni inu mi fi bajẹ si iran na, mo ni, Enia ti o ṣina li aiya ni nwọn, nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi: 11 Awọn ẹniti mo si bura fun ni ibinu mi pe, nwọn ki yio wọ ibi isimi mi.

Psalmu 96

Ọlọrun Ọba Àwọn Ọba

1 Ẹ kọrin titun si Oluwa: ẹ kọrin si Oluwa gbogbo aiye. 2 Ẹ kọrin si Oluwa, fi ibukún fun orukọ rẹ̀; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. 3 Sọ̀rọ ogo rẹ̀ lãrin awọn keferi, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ lãrin gbogbo enia. 4 Nitori ti Oluwa tobi, o si ni iyìn pupọ̀pupọ̀: on li o ni ìbẹru jù gbogbo oriṣa lọ. 5 Nitori pe gbogbo oriṣa orilẹ-ède asan ni nwọn: ṣugbọn Oluwa li o da ọrun. 6 Ọlá ati ọla-nla li o wà niwaju rẹ̀: ipa ati ẹwà mbẹ ninu ibi mimọ́ rẹ̀. 7 Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipá fun Oluwa. 8 Ẹ fi ogo fun orukọ Oluwa: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ̀. 9 Ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́: ẹ wariri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye. 10 Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, Oluwa jọba: nitõtọ a o fi idi aiye mulẹ ti kì yio le yẹ̀: on o fi ododo ṣe idajọ enia. 11 Jẹ ki ọrun ki o yọ̀, jẹ ki inu aiye ki o dùn; jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀. 12 Jẹ ki oko ki o kún fun ayọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: nigbana ni gbogbo igi igbo yio ma yọ̀. 13 Niwaju Oluwa: nitoriti mbọwa, nitori ti mbọwa ṣe idajọ aiye: yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rẹ̀ ṣe.

Psalmu 97

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba; ki aiye ki o yọ̀; jẹ ki inu ọ̀pọlọpọ erekuṣu ki o dùn. 2 Awọsanma ati okunkun yi i ka: ododo ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ̀. 3 Iná ṣaju rẹ̀, o si jo awọn ọta rẹ̀ yika kiri. 4 Manamana rẹ̀ kọ imọlẹ si aiye: aiye ri i, o si wariri. 5 Awọn òke nyọ́ bi ida niwaju Oluwa, niwaju Oluwa gbogbo aiye: 6 Ọrun fi ododo rẹ̀ hàn, gbogbo orilẹ-ède si ri ogo rẹ̀. 7 Oju yio tì gbogbo awọn ti nsìn ere fifin, ẹniti nfi ere ṣe ileri ara wọn: ẹ ma sìn i, gbogbo ẹnyin ọlọrun. 8 Sioni gbọ́, inu rẹ̀ si dùn; awọn ọmọbinrin Juda si yọ̀, Oluwa, nitori idajọ rẹ. 9 Nitoripe Iwọ Oluwa, li o ga jù gbogbo aiye lọ: Iwọ li a gbé ga jù gbogbo oriṣa lọ. 10 Ẹnyin ti o fẹ Oluwa, ẹ korira ibi: o pa ọkàn awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́: o gbà wọn li ọwọ awọn enia buburu. 11 A funrugbin imọlẹ fun olododo, ati inu didùn fun alaiya diduro. 12 Ẹ yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo; ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.

Psalmu 98

Ọlọrun, Ọba gbogbo Ayé

1 Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀. 2 Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi. 3 O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa. 4 Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn. 5 Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́. 6 Pẹlu ipè ati ohùn fere, ẹ ho iho ayọ̀ niwaju Oluwa, Ọba. 7 Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀. 8 Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀. 9 Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.

Psalmu 99

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba; jẹ ki awọn enia ki o wariri: o joko lori awọn kerubu; ki aiye ki o ta gbọ̀ngbọ́n. 2 Oluwa tobi ni Sioni: o si ga jù gbogbo orilẹ-ède lọ. 3 Ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru; mimọ́ li on. 4 Agbara ọba fẹ idajọ pẹlu, iwọ fi idi aiṣegbe mulẹ; iwọ nṣe idajọ ati ododo ni Jakobu. 5 Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ̀: mimọ́ li on. 6 Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ̀, ati Samueli ninu awọn ti npè orukọ rẹ̀: nwọn ke pè Oluwa, o si da wọn lohùn. 7 O ba wọn sọ̀rọ ninu ọwọ̀n awọsanma: nwọn pa ẹri rẹ̀ mọ́ ati ilana ti o fi fun wọn. 8 Iwọ da wọn lohùn, Oluwa Ọlọrun wa: iwọ li Ọlọrun ti o dariji wọn, ti o si san ẹsan iṣẹ wọn. 9 Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sìn nibi òke mimọ́ rẹ̀; nitori Oluwa Ọlọrun wa mimọ́ ni.

Psalmu 100

Orin Ìyìn

1 Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, ẹnyin ilẹ gbogbo. 2 Ẹ fi ayọ̀ sìn Oluwa: ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rẹ̀. 3 Ki ẹnyin ki o mọ̀ pe Oluwa, on li Ọlọrun: on li o dá wa, tirẹ̀ li awa; awa li enia rẹ̀, ati agutan papa rẹ̀. 4 Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀. 5 Nitori ti Oluwa pọ̀ li ore; ãnu rẹ̀ kò nipẹkun; ati otitọ rẹ̀ lati iran-diran.

Psalmu 101

Ìlérí Ọba

1 EMI o kọrin ãnu ati ti idajọ: Oluwa, si ọ li emi o ma kọrin. 2 Emi o ma rìn ìrin mi pẹlu ọgbọ́n li ọ̀na pipé. Nigbawo ni iwọ o tọ̀ mi wá! emi o ma rìn ninu ile mi pẹlu aiya pipé. 3 Emi ki yio gbé ohun buburu siwaju mi: emi korira iṣẹ awọn ti o yapa, kì yio fi ara mọ mi. 4 Aiya ṣiṣo yio kuro lọdọ mi: emi kì yio mọ̀ enia buburu. 5 Ẹnikẹni ti o ba nsọ̀rọ ẹnikeji rẹ̀ lẹhin, on li emi o ke kuro: ẹniti o ni ìwo giga ati igberaga aiya, on li emi kì yio jẹ fun. 6 Oju mi yio wà lara awọn olõtọ, ki nwọn ki o le ma ba mi gbe: ẹniti o ba nrìn li ọ̀na pipé, on ni o ma sìn mi. 7 Ẹniti o ba nṣe ẹ̀tan, kì o gbe inu ile mi: ẹniti o ba nsẹke kì yio duro niwaju mi. 8 Lojojumọ li emi o ma run gbogbo enia buburu ilẹ na; ki emi ki o le ke gbogbo oluṣe buburu kuro ni ilu Oluwa.

Psalmu 102

Adura Olùpọ́njú

1 GBỌ adura mi, Oluwa, ki o si jẹ ki igbe mi ki o wá sọdọ rẹ. 2 Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi li ọjọ ti emi wà ninu ipọnju; dẹ eti rẹ si mi: li ọjọ ti mo ba pè, da mi lohùn-lọgan. 3 Nitori ti ọjọ mi run bi ẹ̃fin, egungun mi si jona bi àro. 4 Aiya mi lù, o si rọ bi koriko; tobẹ̃ ti mo gbagbe lati jẹ onjẹ mi. 5 Nitori ohùn ikerora mi, egungun mi lẹ̀ mọ ẹran-ara mi. 6 Emi dabi ẹiyẹ ofú ni iju: emi dabi owiwi ibi ahoro. 7 Emi nṣọra, emi dabi ologoṣẹ nikan ni ori ile. 8 Awọn ọta mi ngàn mi li ọjọ gbogbo; ati awọn ti nṣe ikanra si mi, nwọn fi mi bu. 9 Emi sa jẹ ẽru bi onjẹ, emi si dà ohun mimu mi pọ̀ pẹlu omije. 10 Nitori ikannu ati ibinu rẹ; nitori iwọ ti gbé mi soke, iwọ si gbé mi ṣanlẹ. 11 Ọjọ mi dabi ojiji ti o nfà sẹhin; emi si nrọ bi koriko. 12 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ni yio duro lailai; ati iranti rẹ lati iran dé iran. 13 Iwọ o dide, iwọ o ṣãnu fun Sioni: nitori igba ati ṣe oju-rere si i, nitõtọ, àkoko na de. 14 Nitori ti awọn iranṣẹ rẹ ṣe inu didùn si okuta rẹ̀, nwọn si kãnu erupẹ rẹ̀. 15 Bẹ̃li awọn keferi yio ma bẹ̀ru orukọ Oluwa, ati gbogbo ọba aiye yio ma bẹ̀ru ogo rẹ. 16 Nigbati Oluwa yio gbé Sioni ró, yio farahan ninu ogo rẹ̀. 17 Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn. 18 Eyi li a o kọ fun iran ti mbọ̀; ati awọn enia ti a o da yio ma yìn Oluwa. 19 Nitori ti o wò ilẹ lati òke ibi-mimọ́ rẹ̀ wá; lati ọrun wá ni Oluwa bojuwo aiye; 20 Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ; 21 Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu. 22 Nigbati a kó awọn enia jọ pọ̀ ati awọn ijọba, lati ma sìn Oluwa. 23 O rẹ̀ agbara mi silẹ li ọ̀na; o mu ọjọ mi kuru. 24 Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ. 25 Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ, 26 Nwọn o ṣegbe, ṣugbọn Iwọ o duro; nitõtọ gbogbo wọn ni yio di ogbó bi aṣọ; bi ẹ̀wu ni iwọ o pàrọ wọn, nwọn o si pàrọ. 27 Ṣugbọn bakanna ni Iwọ, ọdun rẹ kò li opin. 28 Awọn ọmọ awọn iranṣẹ rẹ yio duro pẹ, a o si fi ẹsẹ iru-ọmọ wọn mulẹ niwaju rẹ.

Psalmu 103

Ìfẹ́ Ọlọrun

1 FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́. 2 Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀: 3 Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ, 4 Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade: 5 Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì. 6 Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara. 7 O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli. 8 Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu. 9 On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai. 10 On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa. 11 Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. 12 Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa. 13 Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. 14 Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa. 15 Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ. 16 Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́. 17 Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ: 18 Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn. 19 Oluwa ti pèse itẹ́ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo; 20 Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipa ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohùn ọ̀rọ rẹ̀. 21 Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀ gbogbo; ẹnyin iranṣẹ rẹ̀, ti nṣe ifẹ rẹ̀. 22 Ẹ fi ibukún fun Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ̀ ni ibi gbogbo ijọba rẹ̀: fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.

Psalmu 104

Yíyin Ẹlẹ́dàá

1 FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ. 2 Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita: 3 Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ: 4 Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀. 5 Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai. 6 Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla. 7 Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ. 8 Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn. 9 Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ. 10 Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke. 11 Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn; 12 Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi. 13 O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun. 14 O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá; 15 Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le. 16 Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn. 17 Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀. 18 Awọn òke giga li àbo fun awọn ewurẹ igbẹ: ati awọn apata fun awọn ehoro. 19 O da oṣupa fun akokò: õrùn mọ̀ akokò ìwọ rẹ̀. 20 Iwọ ṣe òkunkun, o si di oru: ninu eyiti gbogbo ẹranko igbo nrìn kiri. 21 Awọn ẹgbọrọ kiniun ndún si ohun ọdẹ wọn, nwọn si nwá onjẹ wọn lọwọ Ọlọrun. 22 Õrùn là, nwọn kó ara wọn jọ, nwọn dubulẹ ninu iho wọn. 23 Enia jade lọ si iṣẹ rẹ̀ ati si lãla rẹ̀ titi di aṣalẹ. 24 Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ. 25 Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla. 26 Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀. 27 Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn. 28 Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn. 29 Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn. 30 Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun. 31 Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀. 32 O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin. 33 Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi. 34 Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa. 35 Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 105

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. 2 Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo. 3 Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. 4 Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. 5 Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀; 6 Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀. 7 Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. 8 O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran. 9 Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; 10 O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye. 11 Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin. 12 Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀. 13 Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran; 14 On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn; 15 Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi, 16 Pẹlupẹlu o pè ìyan wá si ilẹ na: o ṣẹ́ gbogbo ọpá onjẹ. 17 O rán ọkunrin kan lọ siwaju wọn; ani Josefu ti a tà li ẹrú: 18 Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin: 19 Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò. 20 Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. 21 O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀. 22 Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n. 23 Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu. 24 O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ. 25 O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀. 26 O rán Mose iranṣẹ rẹ̀; ati Aaroni, ẹniti o ti yàn. 27 Nwọn fi ọ̀rọ àmi rẹ̀ hán ninu wọn, ati iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu. 28 O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀. 29 O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn. 30 Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn. 31 O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn. 32 O fi yinyin fun wọn fun òjo, ati ọwọ iná ni ilẹ wọn. 33 O si lu àjara wọn, ati igi ọ̀pọtọ wọn; o si dá igi àgbegbe wọn. 34 O sọ̀rọ, eṣú si de ati kokoro li ainiye. 35 Nwọn si jẹ gbogbo ewebẹ ilẹ wọn, nwọn si jẹ eso ilẹ wọn run. 36 O kọlu gbogbo akọbi pẹlu ni ilẹ wọn, ãyo gbogbo ipa wọn. 37 O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀. 38 Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn. 39 O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru. 40 Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun. 41 O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ. 42 Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀. 43 O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀: 44 O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na. 45 Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 106

Oore OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 2 Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn? 3 Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo. 4 Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò. 5 Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ. 6 Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu. 7 Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa. 8 Ṣugbọn o gbà wọn là nitori orukọ rẹ̀, ki o le mu agbara rẹ̀ nla di mimọ̀. 9 O ba Okun pupa wi pẹlu, o si gbẹ: bẹ̃li o sìn wọn là ibu ja bi aginju. 10 O si gbà wọn là li ọwọ ẹniti o korira wọn, o si rà wọn pada li ọwọ ọta nì. 11 Omi si bò awọn ọta wọn: ẹnikan wọn kò si kù. 12 Nigbana ni nwọn gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: nwọn si kọrin iyìn rẹ̀. 13 Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀. 14 Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀. 15 O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn. 16 Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa. 17 Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ. 18 Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu. 19 Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà. 20 Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko. 21 Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti. 22 Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa. 23 Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn. 24 Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: 25 Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa. 26 Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju: 27 Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni. 28 Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú. 29 Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn. 30 Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá. 31 A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai. 32 Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn: 33 Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ. 34 Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn: 35 Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn. 36 Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn. 37 Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa. 38 Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ. 39 Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn. 40 Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀. 41 O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn. 42 Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn. 43 Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn. 44 Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn. 45 O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. 46 O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun. 47 Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ. 48 Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 107

IWE KARUN-UN

Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀

1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 2 Jẹ ki awọn ẹni-irapada Oluwa ki o wi bẹ̃, ẹniti o rà pada kuro ni ọwọ ọta nì. 3 O si kó wọn jọ lati ilẹ wọnnì wá, lati ila-õrun wá, ati lati ìwọ-õrun, lati ariwa, ati lati okun wá. 4 Nwọn nrìn ka kiri li aginju ni ibi ti ọ̀na kò si: nwọn kò ri ilu lati ma gbe. 5 Ebi pa wọn, ongbẹ si gbẹ wọn, o rẹ̀ ọkàn wọn ninu wọn. 6 Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn, 7 O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe. 8 Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! 9 Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa. 10 Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin; 11 Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo: 12 Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ. 13 Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. 14 O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja. 15 Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. 16 Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji. 17 Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn. 18 Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú. 19 Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. 20 O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn. 21 Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. 22 Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀. 23 Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla. 24 Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú. 25 Nitori ti o paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rẹ̀ soke. 26 Nwọn gòke lọ si ọrun, nwọn si tún sọkalẹ lọ si ibú; ọkàn wọn di omi nitori ipọnju. 27 Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin. 28 Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn. 29 O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ. 30 Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn. 31 Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! 32 Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba. 33 O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ; 34 Ilẹ eleso di aṣálẹ̀, nitori ìwa-buburu awọn ti o wà ninu rẹ̀. 35 O sọ aginju di adagun omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi. 36 Nibẹ li o si mu awọn ti ebi npa joko, ki nwọn ki o le tẹ ilu do, lati ma gbe. 37 Lati fún irugbin si oko, ki nwọn si gbìn àgbala ajara, ti yio ma so eso ọ̀pọlọpọ. 38 O busi i fun wọn pẹlu, bẹ̃ni nwọn si pọ̀ si i gidigidi; kò si jẹ ki ẹran-ọ̀sin wọn ki o fà sẹhin. 39 Ẹ̀wẹ, nwọn bùku, nwọn si fà sẹhin, nipa inira, ipọnju, ati ikãnu. 40 O dà ẹ̀gan lù awọn ọmọ-alade, o si mu wọn rìn kiri ni ijù, nibiti ọ̀na kò si. 41 Sibẹ o gbé talaka leke kuro ninu ipọnju, o si ṣe idile wọnni bi agbo-ẹran. 42 Awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ri i, nwọn o si yọ̀: gbogbo ẹ̀ṣẹ ni yio si pa ẹnu rẹ̀ mọ. 43 Ẹniti o gbọ́n, yio si kiyesi nkan wọnyi; awọn na li oye iṣeun-ifẹ Oluwa yio ma ye.

Psalmu 108

Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá

1 OLỌRUN, ọkàn mi ti mura, emi o ma kọrin, emi o si ma fi ogo mi kọrin iyìn. 2 Ji, ohun-elo orin mimọ́ ati dùrù: emi tikarami yio si ji ni kutukutu. 3 Emi o ma yìn ọ, Oluwa, ninu awọn enia: emi o mã kọrin si ọ ninu awọn orilẹ-ède. 4 Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma. 5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye. 6 Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn. 7 Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu. 8 Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi: 9 Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀. 10 Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu? 11 Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ? 12 Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori asan ni iranlọwọ enia. 13 Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin; nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.

Psalmu 109

Ìráhùn Ẹni tí Ó Wà ninu Ìṣòro

1 MÁṢE pa ẹnu rẹ mọ́, Ọlọrun iyìn mi; 2 Nitori ti ẹnu awọn enia buburu, ati ẹnu awọn ẹlẹtan yà silẹ si mi: nwọn ti fi ahọn eke sọ̀rọ si mi. 3 Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi. 4 Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura. 5 Nwọn si fi ibi san ire fun mi, ati irira fun ifẹ mi. 6 Yan enia buburu tì i: jẹ ki Olufisùn ki o duro li ọwọ ọtún rẹ̀. 7 Nigbati a o ṣe idajọ rẹ̀, ki a da a lẹbi: ki adura rẹ̀ ki o di ẹ̀ṣẹ; 8 Ki ọjọ rẹ̀ ki o kuru; ki ẹlomiran ki o rọpo iṣẹ rẹ̀. 9 Ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alainibaba, ki aya rẹ̀ ki o di opó. 10 Jẹ ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alarinkiri, ti nṣagbe: ki nwọn ki o ma tọrọ onjẹ jina si ibi ahoro wọn. 11 Jẹ ki alọnilọwọ-gbà ki o mu ohun gbogbo ti o ni; ki alejo ki o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ. 12 Ki ẹnikẹni ki o má wà lati ṣãnu fun u: má si ṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o si lati ṣe oju rere fun awọn ọmọ rẹ̀ alainibaba. 13 Ki a ke ati ọmọ-de-ọmọ rẹ̀ kuro, ati ni iran ti mbọ̀ ki orukọ wọn ki o parẹ. 14 Ki a ma ranti ẹ̀ṣẹ awọn baba rẹ̀ lọdọ Oluwa; má si jẹ ki a nù ẹ̀ṣẹ iya rẹ̀ nù. 15 Jẹ ki nwọn ki o wà niwaju Oluwa nigbagbogbo, ki o le ke iranti wọn kuro lori ilẹ. 16 Nitori ti kò ranti lati ṣãnu, ṣugbọn o ṣe inunibini si ọkunrin talaka ati olupọnju nì, ki o le pa onirobinujẹ-ọkàn. 17 Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i. 18 Bi o ti fi egun wọ ara rẹ li aṣọ bi ẹwu rẹ̀, bẹ̃ni ki o wá si inu rẹ̀ bi omi, ati bi orõro sinu egungun rẹ̀. 19 Jẹ ki o ri fun u bi aṣọ ti o bò o lara, ati fun àmure ti o fi gbajá nigbagbogbo. 20 Eyi li ère awọn ọta mi lati ọwọ Oluwa wá, ati ti awọn ti nsọ̀rọ ibi si ọkàn mi. 21 Ṣugbọn iwọ ṣe fun mi, Ọlọrun Oluwa, nitori orukọ rẹ: nitoriti ãnu rẹ dara, iwọ gbà mi. 22 Nitoripe talaka ati olupọnju li emi aiya mi si gbọgbẹ ninu mi. 23 Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú. 24 Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra. 25 Emi di ẹ̀gan fun wọn pẹlu: nigbati nwọn wò mi, nwọn mi ori wọn. 26 Ràn mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ. 27 Ki nwọn ki o le mọ̀ pe ọwọ rẹ li eyi; pe Iwọ, Oluwa, li o ṣe e. 28 Nwọn o ma gegun, ṣugbọn iwọ ma sure: nigbati nwọn ba dide, ki oju ki o tì wọn; ṣugbọn iranṣẹ rẹ yio yọ̀. 29 Jẹ ki a fi ìtiju wọ̀ awọn ọta mi li aṣọ, ki nwọn ki o si fi idaru-dapọ̀ wọn bò ara, bi ẹnipe ẹ̀wu. 30 Emi o ma fi ẹnu mi yìn Oluwa gidigidi; nitõtọ, emi o ma yìn i lãrin ọ̀pọ enia. 31 Nitori ti yio duro li ọwọ ọtún olupọnju, lati gbà a lọwọ awọn ti o nda ọkàn rẹ̀ lẹbi.

Psalmu 110

OLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀

1 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọ̀tún mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ. 2 Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ. 3 Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwá li ọjọ ijade-ogun rẹ, ninu ẹwà ìwà-mimọ́: lati inu owurọ wá, iwọ ni ìri ewe rẹ. 4 Oluwa ti bura, kì yio si yi ọkàn pada pe, Iwọ li alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki. 5 Oluwa li ọwọ ọtún rẹ ni yio lù awọn ọba jalẹ li ọjọ ibinu rẹ̀. 6 Yio ṣe idajọ lãrin awọn keferi, yio fi okú kún ibi wọnni; yio fọ́ ori lori ilẹ pupọ̀. 7 Yio ma mu ninu odò na li ọ̀na: nitorina ni yio ṣe gbé ori soke.

Psalmu 111

Yin OLUWA

1 Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia. 2 Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu. 3 Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai. 4 O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu. 5 O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai. 6 O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi. 7 Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju. 8 Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn. 9 O rán idande si awọn enia rẹ̀: o ti paṣẹ majẹmu rẹ̀ lailai: mimọ́ ati ọ̀wọ li orukọ rẹ̀. 10 Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: oye rere ni gbogbo awọn ti npa ofin rẹ̀ mọ́ ni: iyìn rẹ̀ duro lailai.

Psalmu 112

Ayọ̀ Ẹni Rere

1 Ẹ ma yìn Oluwa. Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru Oluwa, ti inu rẹ̀ dùn jọjọ sí ofin rẹ̀. 2 Iru-ọmọ rẹ̀ yio lagbara li aiye: iran ẹni-diduro-ṣinṣin li a o bukún fun. 3 Ọlà ati ọrọ̀ yio wà ni ile rẹ̀: ododo rẹ̀ si duro lailai. 4 Fun ẹni-diduro-ṣinṣin ni imọlẹ mọ́ li òkunkun: olore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o si ṣe olododo. 5 Enia rere fi oju-rere hàn, a si wínni: imoye ni yio ma fi là ọ̀na iṣẹ rẹ̀. 6 Nitoriti a kì yio yi i nipò pada lailai: olododo yio wà ni iranti titi aiye. 7 Kì yio bẹ̀ru ihin buburu: aiya rẹ̀ ti mu ọ̀na kan, o gbẹkẹle Oluwa. 8 Aiya rẹ̀ ti mulẹ, kì yio bẹ̀ru, titi yio fi ri ifẹ rẹ̀ lori awọn ọta rẹ̀. 9 O ti fún ka, o ti fi fun awọn olupọnju; ododo rẹ̀ duro lailai; ọlá li a o fi gbé iwo rẹ̀ ga. 10 Awọn enia buburu yio ri i, inu wọn o si bajẹ; yio pa ehin rẹ̀ keke, yio si yọ́ danu: ifẹ awọn enia buburu yio ṣegbe.

Psalmu 113

Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀

1 Ẹ ma yìn Oluwa! Ẹ ma yìn, ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ẹ ma yìn orukọ Oluwa. 2 Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai. 3 Lati ila-õrun titi o fi de ìwọ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn. 4 Oluwa ga lori gbogbo orilẹ-ède, ogo rẹ̀ si wà lori ọrun. 5 Tali o dabi Oluwa Ọlọrun wa, ti o ngbe ibi giga. 6 Ẹniti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lati wò ohun ti o wà li ọrun ati li aiye! 7 O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbé olupọnju soke lati ori àtan wá; 8 Ki o le mu u joko pẹlu awọn ọmọ-alade, ani pẹlu awọn ọmọ-alade awọn enia rẹ̀. 9 O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!

Psalmu 114

Orin Ìrékọjá

1 NIGBATI Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu àjeji ède enia; 2 Juda di ibi mimọ́ rẹ̀, Israeli di ijọba rẹ̀. 3 Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin. 4 Awọn òke nla nfò bi àgbo, ati awọn òke kekèke bi ọdọ-agutan. 5 Kili o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin? 6 Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekèke bi ọdọ-agutan? 7 Warìri, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu. 8 Ẹniti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.

Psalmu 115

Ọlọrun Òdodo

1 KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ. 2 Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi? 3 Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u. 4 Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia. 5 Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran. 6 Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun. 7 Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade. 8 Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn. 9 Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. 10 Ara-ile Aaroni, gbẹkẹle Oluwa, on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. 11 Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. 12 Oluwa ti nṣe iranti wa: yio bùsi i fun wa: yio bùsi i fun ara-ile Israeli; yio bùsi i fun ara-ile Aaroni. 13 Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba. 14 Oluwa yio mu nyin bisi i siwaju ati siwaju, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin. 15 Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye. 16 Ọrun ani ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn aiye li o fi fun awọn ọmọ enia. 17 Okú kò yìn Oluwa, ati gbogbo awọn ti o sọkalẹ lọ sinu idakẹ. 18 Ṣugbọn awa o ma fi ibukún fun Oluwa, lati igba yi lọ ati si i lailai. Ẹ yìn Oluwa.

Psalmu 116

Orin Ọpẹ́

1 EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi. 2 Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi. 3 Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu. 4 Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi. 5 Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa. 6 Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ. 7 Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ. 8 Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu. 9 Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye. 10 Emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: mo ri ipọnju gidigidi. 11 Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo enia. 12 Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore rẹ̀ si mi? 13 Emi o mu ago igbala, emi o si ma kepè orukọ Oluwa. 14 Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀. 15 Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ̀ li oju Oluwa. 16 Oluwa nitõtọ iranṣẹ rẹ li emi; iranṣẹ rẹ̀ li emi, ati ọmọ iranṣẹ-birin rẹ: iwọ ti tú ìde mi. 17 Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ Oluwa. 18 Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀. 19 Ninu àgbala ile Oluwa, li arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yìn Oluwa.

Psalmu 117

Yíyin OLUWA

1 Ẹ ma yìn Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède gbogbo: ẹ yìn i, ẹnyin enia gbogbo. 2 Nitoriti iṣeun ãnu rẹ̀ pọ̀ si wa: ati otitọ Oluwa duro lailai. Ẹ yìn Oluwa!

Psalmu 118

Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. 2 Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. 3 Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. 4 Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. 5 Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla. 6 Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? 7 Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi. 8 O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle enia lọ. 9 O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle awọn ọmọ-alade lọ. 10 Gbogbo awọn orilẹ-ède yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run. 11 Nwọn yi mi ka kiri; nitõtọ, nwọn yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run. 12 Nwọn yi mi ka kiri bi oyin; a si pa wọn bi iná ẹgún: li orukọ Oluwa emi o sa pa wọn run. 13 Iwọ tì mi gidigidi ki emi ki o le ṣubu; ṣugbọn Oluwa ràn mi lọwọ. 14 Oluwa li agbara ati orin mi, o si di igbala mi. 15 Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. 16 Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. 17 Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa. 18 Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú. 19 Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa. 20 Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle. 21 Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi. 22 Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile. 23 Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa. 24 Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀. 25 Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia. 26 Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá. 27 Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na. 28 Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga. 29 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

Psalmu 119

Òfin OLUWA

1 IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. 2 Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. 3 Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. 4 Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. 5 Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! 6 Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. 7 Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. 8 Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

9 Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 10 Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ. 11 Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ. 12 Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ. 13 Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ. 14 Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. 15 Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. 16 Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.

Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA

17 Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́. 18 Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ. 19 Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi. 20 Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo. 21 Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ. 22 Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́. 23 Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ: 24 Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi.

Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́

25 Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 26 Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ. 27 Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ. 28 Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 29 Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi. 30 Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi. 31 Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi. 32 Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye.

Adura fún Òye

33 Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. 34 Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. 35 Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. 36 Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. 37 Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. 38 Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. 39 Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. 40 Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ.

Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA

41 Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 42 Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ. 43 Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ. 44 Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai. 45 Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ. 46 Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju. 47 Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ. 48 Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.

Igbẹkẹ le ninu Òfin OLUWA

49 Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. 50 Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. 51 Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. 52 Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. 53 Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. 54 Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. 55 Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. 56 Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.

Ìfọkànsí Òfin OLUWA

57 Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́. 58 Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 59 Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ. 60 Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́. 61 Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ. 62 Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ. 63 Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́. 64 Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.

Iyebíye ni Òfin OLUWA

65 Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 66 Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́. 67 Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. 68 Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ. 69 Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo. 70 Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ. 71 O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ. 72 Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ.

Òdodo ni Òfin OLUWA

73 Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ. 74 Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ. 75 Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju. 76 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ. 77 Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi. 78 Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ. 79 Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ. 80 Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi.

Adura Ìdáǹdè

81 Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ. 82 Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu? 83 Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ. 84 Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi? 85 Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ. 86 Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ. 87 Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ. 88 Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́.

Igbagbọ ninu Òfin OLUWA

89 Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. 90 Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. 91 Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. 92 Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. 93 Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye. 94 Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ. 95 Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ. 96 Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi.

Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA

97 Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo. 98 Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai. 99 Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi. 100 Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́. 101 Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́. 102 Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi. 103 Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi! 104 Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo.

Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA

105 Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi. 106 Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́. 107 A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 108 Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ. 109 Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ. 110 Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ. 111 Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi. 112 Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin.

Ààbò ninu Òfin OLUWA

113 Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. 114 Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. 115 Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́. 116 Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi. 117 Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo. 118 Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn. 119 Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ. 120 Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

121 Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi. 122 Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara. 123 Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ. 124 Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ. 125 Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ. 126 Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo. 127 Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ. 128 Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.

Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́

129 Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́. 130 Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe. 131 Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ. 132 Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ. 133 Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi. 134 Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́. 135 Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ. 136 Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.

Òtítọ́ ni Òfin OLUWA

137 Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ. 138 Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi. 139 Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ. 140 Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ. 141 Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ. 142 Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ. 143 Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi. 144 Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè.

Adura Ìdáǹdè

145 Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́. 146 Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́. 147 Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. 148 Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ. 149 Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. 150 Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ. 151 Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ. 152 Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai.

Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́

153 Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ. 154 Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ. 155 Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ. 156 Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. 157 Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ. 158 Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́. 159 Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ. 160 Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai.

Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA

161 Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ. 162 Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ. 163 Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. 164 Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ. 165 Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn. 166 Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ. 167 Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi. 168 Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ.

Adura Ìrànlọ́wọ́

169 Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 170 Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. 171 Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ. 172 Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ. 173 Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ. 174 Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi. 175 Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ. 176 Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.

Psalmu 120

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 NINU ipọnju mi emi kepè Oluwa, o si da mi lohùn. 2 Oluwa, gbà ọkàn mi, lọwọ ète eke, ati lọwọ ahọn ẹ̀tan? 3 Kini ki a fi fun ọ? tabi kini ki a ṣe si ọ, ahọn ẹ̀tan. 4 Ọfà mimu alagbara, ti on ti ẹyin-iná igi juniperi! 5 Egbe ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meṣeki, ti mo joko ninu agọ Kedari! 6 O ti pẹ ti ọkàn mi ti ba ẹniti o korira alafia gbe. 7 Alafia ni mo fẹ: ṣugbọn nigbati mo ba sọ̀rọ, ija ni ti wọn.

Psalmu 121

OLUWA Aláàbò Wa

1 EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa? 2 Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye. 3 On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe. 4 Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn. 5 Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ. 6 Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru. 7 Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́. 8 Oluwa yio pa alọ ati àbọ rẹ mọ́ lati igba yi lọ, ati titi lailai.

Psalmu 122

Ìyìn Jerusalẹmu

1 INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa. 2 Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu. 3 Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan. 4 Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa. 5 Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi. 6 Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere. 7 Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ. 8 Nitori awọn arakunrin ati awọn ẹgbẹ mi, emi o wi nisisiyi pe, Ki alafia ki o wà ninu rẹ! 9 Nitori ile Oluwa Ọlọrun wa, emi o ma wá ire rẹ.

Psalmu 123

Adura Àánú

1 IWỌ ni mo gbé oju mi soke si, iwọ ti ngbe inu ọrun. 2 Kiyesi i, bi oju awọn iranṣẹkunrin ti ima wò ọwọ awọn baba wọn, ati bi oju iranṣẹ-birin ti ima wò ọwọ iya rẹ̀; bẹ̃li oju wa nwò Oluwa Ọlọrun wa, titi yio fi ṣãnu fun wa. 3 Oluwa, ṣãnu fun wa, ṣãnu fun wa: nitori ti a kún fun ẹ̀gan pupọ̀-pupọ̀. 4 Ọkàn wa kún pupọ̀-pupọ̀ fun ẹ̀gan awọn onirera, ati fun ẹ̀gan awọn agberaga.

Psalmu 124

Ọlọrun Aláàbò Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 IBA máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, ki Israeli ki o ma wi nisisiyi; 2 Iba máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, nigbati awọn enia duro si wa: 3 Nigbana ni nwọn iba gbé wa mì lãye, nigbati ibinu nwọn ru si wa: 4 Nigbana li omi wọnni iba bò wa mọlẹ, iṣan omi iba ti bori ọkàn wa: 5 Nigbana li agberaga omi iba bori ọkàn wa. 6 Olubukún li Oluwa, ti kò fi wa fun wọn bi ohun ọdẹ fun ehin wọn. 7 Ọkàn wa yọ bi ẹiyẹ jade kuro ninu okùn apẹiyẹ: okùn já, awa si yọ. 8 Iranlọwọ wa mbẹ li orukọ Oluwa, ti o da ọrun on aiye.

Psalmu 125

Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA

1 AWỌN ti o gbẹkẹle Oluwa yio dabi òke Sioni, ti a kò le ṣi ni idi, bikoṣepe o duro lailai. 2 Bi òke nla ti yi Jerusalemu ka, bẹ̃li Oluwa yi awọn enia rẹ̀ ka lati isisiyi lọ ati titi lailai. 3 Nitori ti ọpá awọn enia buburu kì yio bà le ipin awọn olododo: ki awọn olododo ki o má ba fi ọwọ wọn le ẹ̀ṣẹ. 4 Oluwa ṣe rere fun awọn ẹni-rere, ati fun awọn ti aiya wọn duro ṣinṣin. 5 Bi o ṣe ti iru awọn ti nwọn yà si ipa ọ̀na wiwọ wọn: Oluwa yio jẹ ki wọn lọ pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn alafia yio wà lori Israeli.

Psalmu 126

Ẹkún Di Ayọ̀

1 NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá. 2 Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn. 3 Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀. 4 Oluwa mu ikólọ wa pada, bi iṣan-omi ni gusu. 5 Awọn ti nfi omije fún irugbin yio fi ayọ ka. 6 Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ̀ pada wá, yio si rù iti rẹ̀.

Psalmu 127

Abániṣé ni OLUWA

1 BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan. 2 Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun. 3 Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀. 4 Bi ọfà ti ri li ọwọ alagbara, bẹ̃li awọn ọmọ igbà èwe rẹ. 5 Ibukún ni fun ọkunrin na ti apo rẹ̀ kún fun wọn: oju kì yio tì wọn, ṣugbọn nwọn o ṣẹgun awọn ọta li ẹnu ọ̀na.

Psalmu 128

Ìbẹ̀rù OLUWA lérè

1 IBUKÚN ni fun gbogbo ẹniti o bẹ̀ru Oluwa; ti o si nrìn li ọ̀na rẹ̀. 2 Nitori ti iwọ o jẹ iṣẹ́ ọwọ rẹ: ibukún ni fun ọ: yio si dara fun ọ. 3 Obinrin rẹ yio dabi àjara rere eleso pupọ li arin ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yio dabi igi olifi yi tabili rẹ ka. 4 Kiyesi i, pe bẹ̃li a o busi i fun ọkunrin na, ti o bẹ̀ru Oluwa. 5 Ki Oluwa ki o busi i fun ọ lati Sioni wá, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu li ọjọ aiye rẹ gbogbo. 6 Bẹ̃ni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ: ati alafia lara Israeli.

Psalmu 129

Kí ojú ti ọ̀tá

1 IGBA pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá, ni ki Israeli ki o wi nisisiyi. 2 Igba pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá: sibẹ nwọn kò ti ibori mi. 3 Awọn awalẹ̀ walẹ si ẹhin mi: nwọn si la aporo wọn gigun. 4 Olododo li Oluwa: o ti ke okùn awọn enia buburu kuro. 5 Ki gbogbo awọn ti o korira Sioni ki o dãmu, ki nwọn ki o si yi ẹhin pada. 6 Ki nwọn ki o dabi koriko ori-ile ti o gbẹ danu, ki o to dagba soke: 7 Eyi ti oloko pipa kò kún ọwọ rẹ̀; bẹ̃li ẹniti ndi ití, kò kún apa rẹ̀. 8 Bẹ̃li awọn ti nkọja lọ kò wipe, Ibukún Oluwa ki o pẹlu nyin: awa sure fun nyin li orukọ Oluwa.

Psalmu 130

Adura Ẹlẹ́ṣẹ̀

1 LATI inu ibu wá li emi kepe ọ, Oluwa. 2 Oluwa, gbohùn mi, jẹ ki eti rẹ ki o tẹ́ silẹ si ohùn ẹ̀bẹ mi. 3 Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro? 4 Nitori idariji wà lọdọ rẹ, ki a le ma bẹ̀ru rẹ. 5 Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọ̀rọ rẹ̀ li emi nṣe ireti. 6 Ọkàn mi duro dè Oluwa, jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ, ani jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ. 7 Israeli iwọ ni ireti niti Oluwa: nitori pe lọdọ Oluwa li ãnu wà, ati lọdọ rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ idande wà. 8 On o si da Israeli nidè kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo,

Psalmu 131

Àṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀

1 OLUWA, aiya mi kò gbega, bẹ̃li oju mi kò gbé soke: bẹ̃li emi kò fi ọwọ mi le ọ̀ran nla, tabi le ohun ti o ga jù mi lọ. 2 Nitõtọ emi mu ọkàn mi simi, mo si mu u dakẹjẹ, bi ọmọ ti a ti ọwọ iya rẹ̀ gbà li ẹnu ọmu: ọkàn mi ri bi ọmọ ti a já li ẹnu ọmu. 3 Israeli, iwọ ni ireti lọdọ Oluwa lati isisiyi lọ ati lailai.

Psalmu 132

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi

1 OLUWA, ranti Dafidi ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: 2 Ẹniti o ti bura fun Oluwa, ti o si ṣe ileri ifẹ fun Alagbara Jakobu pe. 3 Nitõtọ, emi kì yio wọ̀ inu agọ ile mi lọ, bẹ̃li emi kì yio gùn ori akete mi; 4 Emi kì yio fi orun fun oju mi, tabi õgbe fun ipenpeju mi, 5 Titi emi o fi ri ibi fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu. 6 Kiyesi i, awa gburo rẹ̀ ni Efrata: awa ri i ninu oko ẹgàn na. 7 Awa o lọ sinu agọ rẹ̀: awa o ma sìn nibi apoti-itisẹ rẹ̀. 8 Oluwa, dide si ibi isimi rẹ; iwọ, ati apoti agbara rẹ. 9 Ki a fi ododo wọ̀ awọn alufa rẹ: ki awọn enia mimọ rẹ ki o ma hó fun ayọ̀. 10 Nitori ti Dafidi iranṣẹ rẹ, máṣe yi oju ẹni-ororo rẹ pada. 11 Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ. 12 Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ́ ati ẹri mi ti emi o kọ́ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ́ rẹ lailai. 13 Nitori ti Oluwa ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rẹ̀. 14 Eyi ni ibi isimi mi lailai: nihin li emi o ma gbe; nitori ti mo fẹ ẹ. 15 Emi o bukún onjẹ rẹ̀ pupọ̀-pupọ̀: emi o fi onjẹ tẹ́ awọn talaka rẹ̀ lọrùn. 16 Emi o si fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ̀: awọn enia mimọ́ rẹ̀ yio ma hó fun ayọ̀. 17 Nibẹ li emi o gbe mu iwo Dafidi yọ, emi ti ṣe ilana fitila kan fun ẹni-ororo mi. 18 Awọn ọta rẹ̀ li emi o fi itiju wọ̀: ṣugbọn lara on tikararẹ̀ li ade rẹ̀ yio ma gbilẹ.

Psalmu 133

Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará

1 KIYESI i, o ti dara o si ti dùn to fun awọn ará lati ma jumọ gbe ni irẹpọ̀. 2 O dabi ororo ikunra iyebiye li ori, ti o ṣàn de irungbọn, ani irungbọn Aaroni: ti o si ṣàn si eti aṣọ rẹ̀; 3 Bi ìri Hermoni ti o ṣàn sori òke Sioni: nitori nibẹ ni Oluwa gbe paṣẹ ibukún, ani ìye lailai.

Psalmu 134

Ẹ yin OLUWA

1 Ẹ kiyesi i, ẹ fi ibukún fun Oluwa, gbogbo ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ti nduro ni ile Oluwa li oru. 2 Ẹ gbé ọwọ nyin soke si ibi-mimọ́, ki ẹ si fi ibukún fun Oluwa. 3 Oluwa ti o da ọrun on aiye, ki o busi i fun ọ lati Sioni wá.

Psalmu 135

Orin Ìyìn

1 Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa. 2 Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa. 3 Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn. 4 Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀. 5 Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ. 6 Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo. 7 O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá. 8 Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko. 9 Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo. 10 Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba. 11 Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani: 12 O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀. 13 Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran. 14 Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, 15 Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia. 16 Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran. 17 Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn. 18 Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn. 19 Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa. 20 Ẹnyin arale Lefi, ẹ fi ibukún fun Oluwa; ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ fi ibukún fun Oluwa. 21 Olubukún li Oluwa, lati Sioni wá, ti ngbe Jerusalemu. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 136

Orin Ọpẹ́

1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 2 Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 3 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 4 Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 5 Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 6 Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 7 Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 8 Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: 9 Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 10 Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 11 O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: 12 Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 13 Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: 14 O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 15 Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 16 Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 17 Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 18 O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 19 Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 20 Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 21 O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 22 Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 23 Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 24 O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. 25 Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai; 26 Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

Psalmu 137

Àwọn Ọmọ Israẹli Kọrin Arò ní Ìgbèkùn

1 LI ẹba odò Babeli, nibẹ li awa gbe joko, awa si sọkun nigbati awa ranti Sioni. 2 Awa fi duru wa kọ́ si ori igi wíllo ti o wà lãrin rẹ̀. 3 Nitoripe nibẹ li awọn ti o kó wa ni igbekun bère orin lọwọ wa; ati awọn ti o ni wa lara bère idaraya wipe; Ẹ kọ orin Sioni kan fun wa. 4 Awa o ti ṣe kọ orin Oluwa ni ilẹ àjeji? 5 Jerusalemu, bi emi ba gbagbe rẹ, jẹ ki ọwọ ọtún mi ki o gbagbe ìlò rẹ̀. 6 Bi emi kò ba ranti rẹ, jẹ ki ahọn mi ki o lẹ̀ mọ èrìgì mi; bi emi kò ba fi Jerusalemu ṣaju olori ayọ̀ mi gbogbo. 7 Oluwa, ranti ọjọ Jerusalemu lara awọn ọmọ Edomu, awọn ẹniti nwipe, Wó o palẹ, wó o palẹ, de ipilẹ rẹ̀! 8 Iwọ, ọmọbinrin Babeli, ẹniti a o parun; ibukún ni fun ẹniti o san a fun ọ bi iwọ ti hù si wa. 9 Ibukún li ẹniti o mu, ti o si fi ọmọ wẹwẹ rẹ ṣán okuta.

Psalmu 138

Adura Ọpẹ́

1 EMI o ma yìn ọ tinu-tinu mi gbogbo; niwaju awọn oriṣa li emi o ma kọrin iyìn si ọ. 2 Emi o ma gbadura siha tempili mimọ́ rẹ, emi o si ma yìn orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọ̀rọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ. 3 Li ọjọ ti mo kepè, iwọ da mi lohùn, iwọ si fi ipa mu mi lara le li ọkàn mi. 4 Gbogbo awọn ọba aiye yio yìn ọ, Oluwa, nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ. 5 Nitõtọ, nwọn o ma kọrin ni ipa-ọ̀na Oluwa: nitori pe nla li ogo Oluwa. 6 Bi Oluwa tilẹ ga, sibẹ o juba awọn onirẹlẹ; ṣugbọn agberaga li o mọ̀ li òkere rére. 7 Bi emi tilẹ nrìn ninu ipọnju, iwọ ni yio sọ mi di ãye: iwọ o nà ọwọ rẹ si ibinu awọn ọta mi, ọwọ ọtún rẹ yio si gbà mi. 8 Oluwa yio ṣe ohun ti iṣe ti emi li aṣepe: Oluwa, ãnu rẹ duro lailai: máṣe kọ̀ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.

Psalmu 139

Ọlọrun Olùmọ̀ràn Ọkàn

1 OLUWA, iwọ ti wadi mi, iwọ si ti mọ̀ mi. 2 Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére. 3 Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ. 4 Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata. 5 Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi. 6 Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ. 7 Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ? 8 Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ. 9 Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; 10 Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu. 11 Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka. 12 Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ. 13 Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi. 14 Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju. 15 Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye. 16 Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi. 17 Ọlọrun, ìro inu rẹ ti ṣe iye-biye to fun mi, iye wọn ti pọ̀ to! 18 Emi iba kà wọn, nwọn jù iyanrin lọ ni iye: nigbati mo ba jí, emi wà lọdọ rẹ sibẹ. 19 Ọlọrun iba jẹ pa enia buburu nitõtọ: nitorina kuro lọdọ mi ẹnyin ọkunrin ẹ̀jẹ. 20 Ẹniti nfi inu buburu sọ̀rọ si ọ, awọn ọta rẹ npè orukọ rẹ li asan! 21 Oluwa, njẹ emi kò korira awọn ti o korira rẹ? njẹ inu mi kò ha si bajẹ si awọn ti o dide si ọ? 22 Emi korira wọn li àkotan: emi kà wọn si ọta mi. 23 Ọlọrun, wadi mi, ki o si mọ̀ aiya mi: dán mi wò, ki o si mọ̀ ìro-inu mi: 24 Ki o si wò bi ipa-ọ̀na buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọ̀na ainipẹkun.

Psalmu 140

Adura Ààbò

1 OLUWA gbà mi lọwọ ọkunrin buburu nì, yọ mi lọwọ ọkunrin ìka nì; 2 Ẹniti nrò ìwa-buburu ni inu wọn; nigbagbogbo ni nwọn nrú ìja soke si mi. 3 Nwọn ti pọ́n ahọn wọn bi ejo; oro pãmọlẹ mbẹ li abẹ ète wọn. 4 Oluwa, pa mi mọ́ kuro lọwọ enia buburu; yọ mi kuro lọwọ ọkunrin ìka nì; ẹniti o ti pinnu rẹ̀ lati bì ìrin mi ṣubu. 5 Awọn agberaga dẹ pakute silẹ fun mi, ati okùn; nwọn ti nà àwọn lẹba ọ̀na; nwọn ti kẹkùn silẹ fun mi. 6 Emi wi fun Oluwa pe, iwọ li Ọlọrun mi: Oluwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi. 7 Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi, iwọ li o bò ori mi mọlẹ li ọjọ ìja. 8 Oluwa, máṣe fi ifẹ enia buburu fun u: máṣe kún ọgbọ́n buburu rẹ̀ lọwọ: ki nwọn ki o má ba gbé ara wọn ga. 9 Bi o ṣe ti ori awọn ti o yi mi ká kiri ni, jẹ ki ìka ète ara wọn ki o bò wọn mọlẹ. 10 A o da ẹyin iná si wọn lara: on o wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin, ki nwọn ki o má le dide mọ́. 11 Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu. 12 Emi mọ̀ pe, Oluwa yio mu ọ̀ran olupọnju duro, ati are awọn talaka. 13 Nitõtọ awọn olododo yio ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ: awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ma gbe iwaju rẹ.

Psalmu 141

Adura Ààbò

1 OLUWA, emi kigbe pè ọ: yara si ọdọ mi; fi eti si ohùn mi, nigbati mo ba nkepè ọ. 2 Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ bi ẹbọ turari; ati igbé ọwọ mi soke bi ẹbọ aṣãlẹ. 3 Oluwa, fi ẹṣọ́ siwaju ẹnu mi; pa ilẹkun ète mi mọ́. 4 Máṣe fà aiya mi si ohun ibi kan, lati ma ba awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ṣiṣẹ buburu; má si jẹ ki emi ki o jẹ ninu ohun didùn wọn. 5 Jẹ ki olododo ki o lù mi; iṣeun ni yio jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yio jasi, ti kì yio fọ́ mi lori: sibẹ adura mi yio sa wà nitori jamba wọn. 6 Nigbati a ba bì awọn onidajọ wọn ṣubu ni ibi okuta, nwọn o gbọ́ ọ̀rọ mi, nitori ti o dùn. 7 Egungun wa tàn kalẹ li ẹnu isà-òkú, ẹniti o la aporo sori ilẹ. 8 Ṣugbọn oju mi mbẹ lara rẹ; Ọlọrun Oluwa, lọdọ rẹ ni igbẹkẹle mi wà; máṣe tú ọkàn mi dà silẹ. 9 Pa mi mọ́ kuro ninu okùn ti nwọn dẹ silẹ fun mi, ati ikẹkùn awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. 10 Jẹ ki awọn enia buburu ki o bọ́ sinu àwọn ara wọn, nigbati emi ba kọja lọ.

Psalmu 142

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA ni mo fi ohùn mi kigbe pè; ohùn mi ni mo fi mbẹ̀bẹ mi si Oluwa. 2 Emi tú aroye mi silẹ niwaju rẹ̀; emi fi iṣẹ́ mi hàn niwaju rẹ̀. 3 Nigbati ọkàn mi rẹ̀wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ̀ ipa-ọ̀na mi. Li ọ̀na ti emi nrìn ni nwọn dẹkùn silẹ fun mi nikọ̀kọ. 4 Emi wò ọwọ ọtún, mo si ri pe, kò si ẹnikan ti o mọ̀ mi: àbo dẹti fun mi; kò si ẹniti o nãni ọkàn mi. 5 Oluwa, iwọ ni mo kigbe pè: emi wipe, iwọ li àbo mi ati ipin mi ni ilẹ alãye. 6 Fiyesi igbe mi: nitori ti a rẹ̀ mi silẹ gidigidi: gbà mi lọwọ awọn oninu-nibini mi. Nitori nwọn lagbara ju mi lọ. 7 Mu ọkàn mi jade kuro ninu tubu, ki emi ki o le ma yìn orukọ rẹ; awọn olododo yio yi mi ka kiri; nitori iwọ o fi ọ̀pọlọpọ ba mi ṣe.

Psalmu 143

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, gbọ́ adura mi, fi eti si ẹ̀bẹ mi; ninu otitọ rẹ dá mi lohùn ati ninu ododo rẹ. 2 Ki o má si ba ọmọ-ọdọ rẹ lọ sinu idajọ, nitori ti kò si ẹniti o wà lãye ti a o dalare niwaju rẹ. 3 Nitori ti ọta ti ṣe inunibini si ọkàn mi; o ti lù ẹmi mi bolẹ; o ti mu mi joko li òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. 4 Nitorina li ẹmi mi ṣe rẹ̀wẹsi ninu mi; òfo fò aiya mi ninu mi. 5 Emi ranti ọjọ atijọ; emi ṣe àṣaro iṣẹ rẹ gbogbo, emi nronu iṣẹ ọwọ rẹ. 6 Emi nà ọwọ mi si ọ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi bi ilẹ gbigbẹ. 7 Oluwa, gbọ́ temi nisisiyi; o rẹ̀ ọkàn mi tan; máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi, ki emi ki o má bà dabi awọn ti o lọ sinu ihò. 8 Mu mi gbọ́ iṣeun-ifẹ rẹ li owurọ; nitori iwọ ni mo gbẹkẹle: mu mi mọ̀ ọ̀na ti emi iba ma tọ̀; nitori mo gbé ọkàn mi soke si ọ. 9 Oluwa, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: ọdọ rẹ ni mo sa pamọ́ si. 10 Kọ́ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹju. 11 Oluwa, sọ mi di ãye nitori orukọ rẹ: ninu ododo rẹ mu ọkàn mi jade ninu iṣẹ́. 12 Ati ninu ãnu rẹ ke awọn ọta mi kuro, ki o si run gbogbo awọn ti nni ọkàn mi lara: nitori pe iranṣẹ rẹ li emi iṣe.

Psalmu 144

Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 OLUBUKÚN li oluwa apata mi, ẹniti o kọ́ ọwọ mi li ogun, ati ika mi ni ìja: 2 Õre mi, ati odi-agbara mi; ile-iṣọ giga, ati olugbala mi; asà mi, ati ẹniti mo gbẹkẹle; eniti o tẹri awọn enia mi ba labẹ mi. 3 Oluwa, kili enia, ti iwọ fi nkiye si i! tabi ọmọ enia, ti iwọ fi nronú rẹ̀! 4 Enia dabi asan: bi ojìji ti nkọja lọ li ọjọ rẹ̀. 5 Oluwa, tẹ̀ ọrun rẹ ba, ki o si sọ̀kalẹ: tọ́ awọn òke nla, nwọn o si ru ẽfin. 6 Kọ manamana jade, ki o si tú wọn ka: ta ọfà rẹ ki o si dà wọn rú. 7 Rán ọwọ rẹ lati òke wá; yọ mi, ki o si gbà mi kuro ninu omi nla, li ọwọ awọn ọmọ àjeji. 8 Ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ọwọ ọtún wọn si jẹ ọwọ ọtún eke. 9 Ọlọrun, emi o kọ orin titun si ọ: lara ohun ọnà orin olokùn mẹwa li emi o kọrin iyìn si ọ. 10 On li o nfi igbala fun awọn ọba: ẹniti o gbà Dafidi iranṣẹ rẹ̀ lọwọ idà ipanilara. 11 Yọ mi, ki o si gbà mi lọwọ awọn ọmọ àjeji, ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ati ọwọ ọtún wọn jẹ ọwọ ọtún eke: 12 Ki awọn ọmọkunrin wa, ki o dabi igi gbigbin ti o dagba ni igba-ewe wọn; ki awọn ọmọbinrin wa ki o le dabi ọwọ̀n igun-ile, ti a ṣe lọnà bi afarawe ãfin. 13 Ki aká wa ki o le kún, ki o ma funni li oniruru iṣura: ki awọn agutan wa ki o ma bi ẹgbẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun mẹwa ni igboro wa: 14 Ki awọn malu wa ki o le rẹrù; ki o má si ikọlù, tabi ikolọ jade: ki o má si aroye ni igboro wa. 15 Ibukún ni fun awọn enia, ti o mbẹ ni iru ìwa bẹ̃: nitõtọ, ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun Oluwa iṣe.

Psalmu 145

Orin Ìyìn

1 EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai. 2 Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai. 3 Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀. 4 Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ. 5 Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ. 6 Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ. 7 Nwọn o ma sọ̀rọ iranti ore rẹ pupọ̀-pupọ̀, nwọn o si ma kọrin ododo rẹ. 8 Olore-ọfẹ li Oluwa, o kún fun ãnu; o lọra lati binu, o si li ãnu pupọ̀. 9 Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo. 10 Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ. 11 Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ: 12 Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo, 13 Ijọba rẹ ijọba aiye-raiye ni, ati ijọba rẹ lati iran-diran gbogbo. 14 Oluwa mu gbogbo awọn ti o ṣubu ró; o si gbé gbogbo awọn ti o tẹriba dide. 15 Oju gbogbo enia nwò ọ; iwọ si fun wọn li onjẹ wọn li akokò rẹ̀. 16 Iwọ ṣi ọwọ rẹ, iwọ si tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alãye lọrùn. 17 Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo. 18 Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ. 19 Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn. 20 Oluwa da gbogbo awọn ti o fẹ ẹ si: ṣugbọn gbogbo enia buburu ni yio parun. 21 Ẹnu mi yio ma sọ̀rọ iyìn Oluwa: ki gbogbo enia ki o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́ lai ati lailai.

Psalmu 146

Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Fi iyìn fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. 2 Nigbati mo wà lãye li emi o ma fi iyìn fun Oluwa: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi, nigbati mo wà. 3 Ẹ máṣe gbẹkẹ nyin le awọn ọmọ-alade, ani le ọmọ-enia, lọwọ ẹniti kò si iranlọwọ. 4 Ẹmi rẹ̀ jade lọ, o pada si erupẹ rẹ̀; li ọjọ na gan, ìro inu rẹ̀ run. 5 Ibukún ni fun ẹniti o ni Ọlọrun Jakobu fun iranlọwọ rẹ̀, ireti ẹniti mbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀: 6 Ẹniti o da ọrun on aiye, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹniti o pa otitọ mọ́ titi aiye: 7 Ẹniti o nṣe idajọ fun ẹni-inilara: ẹniti o nfi onjẹ fun ẹniti ebi npa. Oluwa tú awọn aratubu silẹ: 8 Oluwa ṣi oju awọn afọju: Oluwa gbé awọn ti a tẹ̀ lori ba dide; Oluwa fẹ awọn olododo: 9 Oluwa pa awọn alejo mọ́; o tù awọn alainibaba ati opo lara: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio darú. 10 Oluwa yio jọba lailai, ani Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni, lati iran-diran gbogbo. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 147

Ọlọrun Alágbára

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa: nitori ohun rere ni lati ma kọ orin iyìn si Ọlọrun wa: nitori ti o dùn, iyìn si yẹ. 2 Oluwa li o kọ́ Jerusalemu: on li o kó awọn ifọnkalẹ Israeli jọ. 3 O mu awọn onirora aiya lara da: o di ọgbẹ wọn: 4 O ka iye awọn ìrawọ; o si sọ gbogbo wọn li orukọ. 5 Oluwa wa tobi, ati alagbara nla: oye rẹ̀ kò li opin. 6 Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ. 7 Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru: 8 Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun, ẹniti o pèse òjo fun ilẹ, ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla. 9 O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún. 10 Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin. 11 Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀. 12 Yìn Oluwa, iwọ Jerusalemu; yìn Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni. 13 Nitori ti o ti mu ọpá-idabu ẹnu-bode rẹ le; o ti busi i fun awọn ọmọ rẹ ninu rẹ. 14 O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ. 15 O rán aṣẹ rẹ̀ jade wá si aiye; ọ̀rọ rẹ̀ sure tete. 16 O fi òjo-didì funni bi irun-agutan, o si fún ìri-didì ká bi ẽrú. 17 O dà omi didì rẹ̀ bi òkele; tali o le duro niwaju otutu rẹ̀. 18 O rán ọ̀rọ rẹ̀ jade, o si mu wọn yọ́; o mu afẹfẹ rẹ̀ fẹ, omi si nṣàn. 19 O fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli. 20 Kò ba orilẹ-ède kan ṣe bẹ̃ ri; bi o si ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, nwọn kò mọ̀ wọn. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 148

Kí gbogbo ẹ̀dá Yin OLUWA

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga. 2 Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀. 3 Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ. 4 Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun. 5 Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn. 6 O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja. 7 Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi; 8 Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; 9 Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari; 10 Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò; 11 Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye; 12 Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo enia ati awọn ọmọde; 13 Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun. 14 O si gbé iwo kan soke fun awọn enia rẹ̀, iyìn fun gbogbo enia mimọ́ rẹ̀; ani awọn ọmọ Israeli, awọn enia ti o sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 149

Orin Ìyìn sí OLUWA

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, ati iyìn rẹ̀ ninu ijọ awọn enia-mimọ́. 2 Jẹ ki Israeli ki o yọ̀ si ẹniti o dá a; jẹ ki awọn ọmọ Sioni ki o kún fun ayọ̀ si Ọba wọn. 3 Jẹ ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ̀ ninu ijó: jẹ ki nwọn ki o fi ìlu ati dùru kọrin iyìn si i. 4 Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà. 5 Jẹ ki awọn enia mimọ́ ki o kún fun ayọ̀ ninu ogo; ki nwọn ki o mã kọrin kikan lori ẹni wọn. 6 Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn; 7 Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia. 8 Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn; 9 Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Psalmu 150

Ẹ yin OLUWA

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Ọlọrun ninu ibi mimọ́ rẹ̀; yìn i ninu ofurufu oju-ọrun agbara rẹ̀. 2 Yìn i nitori iṣẹ agbara rẹ̀: yìn i gẹgẹ bi titobi nla rẹ̀. 3 Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i. 4 Fi ìlu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i. 5 Ẹ yìn i lara aro olohùn òke: ẹ yìn i lara aro olohùn goro: 6 Jẹ ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yìn Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Owe 1

Anfaani Àwọn Owe

1 OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli; 2 Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye; 3 Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe; 4 Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu. 5 Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n: 6 Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn.

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́

7 Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́. 8 Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: 9 Nitoripe awọn ni yio ṣe ade ẹwà fun ori rẹ, ati ọṣọ́ yi ọrùn rẹ ka. 10 Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà. 11 Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi. 12 Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho: 13 Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa: 14 Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan: 15 Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn. 16 Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ. 17 Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ. 18 Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn. 19 Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na.

Ọgbọ́n Ń pè

20 Ọgbọ́n nkigbe lode; o nfọhùn rẹ̀ ni igboro: 21 O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọ̀rọ rẹ̀ wipe, 22 Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọ̀kan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọ̀kan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu ẹ̀gan wọn, ati ti awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ? 23 Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o dà ẹmi mi sinu nyin, emi o fi ọ̀rọ mi hàn fun nyin. 24 Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ̀; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si: 25 Ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi: 26 Emi pẹlu o rẹrin idãmu nyin; emi o ṣe ẹ̀fẹ nigbati ibẹ̀ru nyin ba de; 27 Nigbati ibẹ̀ru nyin ba de bi ìji, ati idãmu nyin bi afẹyika-ìji; nigbati wahala ati àrodun ba de si nyin. 28 Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi: 29 Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa. 30 Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi. 31 Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn. 32 Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run. 33 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.

Owe 2

Èrè Tó Wà ninu Ọgbọ́n

1 ỌMỌ mi, bi iwọ ba fẹ igba ọ̀rọ mi, ki iwọ si pa ofin mi mọ́ pẹlu rẹ. 2 Ti iwọ dẹti rẹ silẹ si ọgbọ́n, ti iwọ si fi ọkàn si oye; 3 Ani bi iwọ ba nke tọ̀ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye; 4 Bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ́; 5 Nigbana ni iwọ o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun. 6 Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá. 7 O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede. 8 O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́. 9 Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere. 10 Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ; 11 Imoye yio pa ọ mọ́, oye yio si ma ṣọ́ ọ: 12 Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida; 13 Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun; 14 Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu; 15 Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn: 16 Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni; 17 Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀. 18 Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú. 19 Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye. 20 Ki iwọ ki o le ma rin li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si pa ọ̀na awọn olododo mọ́. 21 Nitoripe ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rẹ̀. 22 Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.

Owe 3

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́

1 ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́. 2 Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. 3 Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ: 4 Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere, ati ọ̀na rere loju Ọlọrun ati enia. 5 Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ. 6 Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ. 7 Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi. 8 On o ṣe ilera si idodo rẹ, ati itura si egungun rẹ. 9 Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: 10 Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun. 11 Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ: 12 Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si. 13 Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. 14 Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. 15 O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. 16 Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. 17 Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia. 18 Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin. 19 Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun. 20 Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ. 21 Ọmọ mi, máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ: pa ọgbọ́n ti o yè, ati imoye mọ́: 22 Bẹ̃ni nwọn o ma jẹ ìye si ọkàn rẹ, ati ore-ọfẹ si ọrùn rẹ. 23 Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ. 24 Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bẹ̀ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn. 25 Máṣe fòya ẹ̀ru ojijì, tabi idahoro awọn enia buburu, nigbati o de. 26 Nitori Oluwa ni yio ṣe igbẹkẹle rẹ, yio si pa ẹsẹ rẹ mọ́ kuro ninu atimu. 27 Máṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹniti iṣe tirẹ̀, bi o ba wà li agbara ọwọ rẹ lati ṣe e. 28 Máṣe wi fun ẹnikeji rẹ pe, Lọ, ki o si pada wá, bi o ba si di ọla, emi o fi fun ọ; nigbati iwọ ni i li ọwọ rẹ. 29 Máṣe gbìro buburu si ọmọnikeji rẹ, bi on ti joko laibẹ̀ru lẹba ọdọ rẹ. 30 Máṣe ba enia jà lainidi, bi on kò ba ṣe ọ ni ibi. 31 Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀. 32 Nitoripe irira li ẹlẹgan loju Oluwa; ṣugbọn aṣiri rẹ̀ wà pẹlu awọn olododo. 33 Egún Oluwa mbẹ ni ile awọn enia buburu: ṣugbọn o bukún ibujoko awọn olõtọ. 34 Nitõtọ o ṣe ẹ̀ya si awọn ẹlẹya: ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ. 35 Awọn ọlọgbọ́n ni yio jogun ogo: ṣugbọn awọn aṣiwere ni yio ru itiju wọn.

Owe 4

Anfaani Tí Ó Wà ninu Ọgbọ́n

1 ENYIN ọmọ, ẹ gbọ́ ẹkọ́ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ̀ oye. 2 Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ̀ ofin mi silẹ. 3 Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-ikẹ́ ati olufẹ li oju iya mi. 4 On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè. 5 Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. 6 Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́. 7 Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye. 8 Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra. 9 On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ. 10 Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ. 11 Emi ti kọ́ ọ li ọ̀na ọgbọ́n; emi ti mu ọ tọ̀ ipa-ọ̀na titọ. 12 Nigbati iwọ nrìn, ọ̀na rẹ kì yio há fun àye; nigbati iwọ nsare, iwọ kì yio fi ẹsẹ kọ. 13 Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ. 14 Máṣe bọ si ipa-ọ̀na enia buburu, má si ṣe rìn li ọ̀na awọn enia ibi. 15 Yẹ̀ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rẹ̀, yẹ̀ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ. 16 Nitoriti nwọn kì isùn bikoṣepe nwọn hùwa buburu; orun wọn a si dá, bikoṣepe nwọn ba mu enia ṣubu. 17 Nitori ti nwọn njẹ onjẹ ìwa-ika, nwọn si nmu ọti-waini ìwa-agbara. 18 Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan. 19 Ọna awọn enia buburu dabi òkunkun: nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn ndugbolu. 20 Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi. 21 Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ. 22 Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn. 23 Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye. 24 Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète ẹ̀tan jina rére kuro lọdọ rẹ. 25 Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ. 26 Ronu ipa-ọ̀na rẹ, gbogbo ọ̀na rẹ ni yio si fi idi mulẹ. 27 Máṣe yà si apa ọtun tabi si apa òsi, ṣi ẹsẹ rẹ kuro ninu ibi.

Owe 5

Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè

1 ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi. 2 Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́. 3 Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ: 4 Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji. 5 Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú. 6 Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀. 7 Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. 8 Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀: 9 Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka; 10 Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo. 11 Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun. 12 Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: 13 Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi. 14 Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ. 15 Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ. 16 Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita. 17 Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ. 18 Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. 19 Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba. 20 Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra? 21 Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo. 22 Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu. 23 Yio kú li aigbà ẹkọ́, ati ninu ọ̀pọlọpọ were rẹ̀ yio si ma ṣina kiri.

Owe 6

Àwọn Ìkìlọ̀ Mìíràn

1 ỌMỌ mi, bi iwọ ba ṣe onigbọwọ fun ọrẹ́ rẹ, bi iwọ ba jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun ajeji enia. 2 Bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ dẹkùn fun ọ, bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ mu ọ. 3 Njẹ, sa ṣe eyi, ọmọ mi, ki o si gbà ara rẹ silẹ nigbati iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ́ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ, ki iwọ ki o si tù ọrẹ́ rẹ. 4 Máṣe fi orun fun oju rẹ, tabi õgbe fun ipenpeju rẹ. 5 Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ. 6 Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rẹ̀ ki iwọ ki o si gbọ́n: 7 Ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso. 8 Ti npese onjẹ rẹ̀ ni igba-ẹ̀run, ti o si nkó onjẹ rẹ̀ jọ ni ìgba ikore. 9 Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ? 10 Orun diẹ si i, õgbe diẹ si i, ikawọkòpọ lati sùn diẹ: 11 Bẹ̃ni òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn àjo, ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun. 12 Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke. 13 O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe; 14 Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ. 15 Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe. 16 Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: 17 Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, 18 Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika, 19 Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin.

Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè

20 Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: 21 Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ. 22 Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ. 23 Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye: 24 Lati pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin buburu nì, lọwọ ahọn ìpọnni ajeji obinrin. 25 Máṣe ifẹkufẹ li aiya rẹ si ẹwà rẹ̀; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki on ki o fi ipenpeju rẹ̀ mu ọ. 26 Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara. 27 Ọkunrin le gbé iná lé aiya rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o má jona? 28 Ẹnikan ha le gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona? 29 Bẹ̃li ẹniti o wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ bà a, kì yio wà li ailẹṣẹ̀. 30 Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a; 31 Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan. 32 Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run. 33 Ọgbẹ ati àbuku ni yio ni; ẹ̀gan rẹ̀ kì yio si parẹ́ kuro. 34 Nitori owú ni ibinu ọkunrin: nitorina kì yio dasi li ọjọ ẹsan. 35 On kì yio nani owo idande, bẹ̃ni inu rẹ̀ kì yio yọ́, bi iwọ tilẹ sọ ẹ̀bun di pipọ.

Owe 7

1 ỌMỌ mi, pa ọ̀rọ mi mọ́, ki o si fi ofin mi ṣe ìṣura ṣura pẹlu rẹ. 2 Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; ati aṣẹ mi bi ọmọloju rẹ. 3 Dì wọn mọ ika rẹ, kọ wọn si wala aiya rẹ. 4 Wi fun ọgbọ́n pe, Iwọ li arabinrin mi; ki o si pe oye ni ibatan rẹ obinrin: 5 Ki nwọn ki o le pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin ẹlomiran, lọwọ ajeji ti nfi ọ̀rọ rẹ̀ ṣe ipọnni.

Obinrin Oníṣekúṣe

6 Li oju ferese ile mi li emi sa bojuwò lãrin ferese mi. 7 Mo si ri ninu awọn òpe, mo kiyesi ninu awọn ọmọkunrin, ọmọkunrin kan ti oye kù fun, 8 O nkọja lọ ni igboro li eti igun ile rẹ̀; o si lọ si ọ̀na ile rẹ̀, 9 Ni wiriwiri imọlẹ, li aṣãlẹ, li oru dudu ati òkunkun: 10 Si kiyesi i, obinrin kan pade rẹ̀, o wọ aṣọ panṣaga, alarekereke aiya. 11 (O jẹ alariwo ati alagidi; ẹsẹ rẹ̀ kì iduro ni ile rẹ̀. 12 Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.) 13 Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe, 14 Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi. 15 Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ. 16 Emi ti fi aṣọ titẹ ọlọnà tẹ́ akete mi, ọlọnà finfin ati aṣọ ọ̀gbọ daradara ti Egipti. 17 Emi ti fi turari olõrùn didùn ti mirra, aloe, ati kinnamoni si akete mi. 18 Wá, jẹ ki a gbà ẹkún ifẹ wa titi yio fi di owurọ, jẹ ki a fi ifẹ tù ara wa lara. 19 Nitoripe bãle kò si ni ile, o re àjo ọ̀na jijin: 20 O mu àsuwọn owo kan lọwọ rẹ̀, yio si de li oṣupa arànmọju. 21 Ọ̀rọ rẹ̀ daradara li o fi mu u fẹ, ipọnni ète rẹ̀ li o fi ṣẹ́ ẹ li apa. 22 On si tọ̀ ọ lọ lẹsẹkanna bi malu ti nlọ si ibupa, tabi bi aṣiwere ti nlọ si ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́. 23 Titi ọfà fi gún u li ẹ̀dọ̀; bi ẹiyẹ ti nyara bọ sinu okùn, ti kò si mọ̀ pe fun ẹmi on ni. 24 Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi. 25 Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀. 26 Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa. 27 Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú.

Owe 8

Yíyin Ọgbọ́n

1 ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi? 2 O duro li ori ibi-giga wọnni, lẹba ọ̀na, nibi ipa-ọ̀na wọnni. 3 O nke li ẹnu-ọ̀na, ati ni ibode ilu, li atiwọ̀ oju ilẹkun. 4 Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia. 5 Ẹnyin òpe, ẹ mọ̀ ọgbọ́n: ati ẹnyin aṣiwere ki ẹnyin ki o ṣe alaiya oye. 6 Ẹ gbọ́, nitori ti emi o sọ̀rọ ohun ti o dara, ati ṣiṣi ète mi yio sọ̀rọ ohun titọ. 7 Nitori ti ẹnu mi yio sọ̀rọ otitọ; ìwa-buburu si ni irira fun ète mi. 8 Ninu ododo ni gbogbo ọ̀rọ ẹnu mi; kò si ẹ̀tan kan tabi arekereke ninu wọn. 9 Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri. 10 Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ. 11 Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. 12 Emi ọgbọ́n li o mba imoye gbe, emi ìmọ si ri imoye ironu. 13 Ibẹ̀ru Oluwa ni ikorira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀na ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo korira. 14 Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara. 15 Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ. 16 Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye. 17 Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi. 18 Ọrọ̀ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ̀ daradara ati ododo. 19 Ere mi ta wura yọ; nitõtọ, jù wura daradara lọ: ati ọrọ̀ mi jù fadaka àṣayan lọ. 20 Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ: 21 Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn. 22 Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ. 23 A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà. 24 Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ. 25 Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi: 26 Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye. 27 Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun. 28 Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu: 29 Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye. 30 Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀; 31 Emi nyọ̀ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didùn-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia. 32 Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi: 33 Gbọ́ ẹkọ́, ki ẹnyin ki o si gbọ́n, má si ṣe jẹ ki o lọ. 34 Ibukún ni fun ẹniti o gbọ́ temi, ti o nṣọ́ ẹnu-ọ̀na mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi. 35 Nitoripe ẹniti o ri mi, o ri ìye, yio si ri ojurere Oluwa. 36 Ṣugbọn ẹniti o ṣẹ̀ mi, o ṣe ọkàn ara rẹ̀ nikà: gbogbo awọn ti o korira mi, nwọn fẹ ikú.

Owe 9

Ọgbọ́n ati Wèrè

1 ỌGBỌ́N ti kọ́ ile rẹ̀, o si gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ meje: 2 O ti pa ẹran rẹ̀; o ti ṣe àdalu ọti-waini rẹ̀; o si ti tẹ́ tabili rẹ̀. 3 O ti ran awọn ọmọbinrin rẹ̀ jade, o nke lori ibi giga ilu, pe, 4 Ẹnikẹni ti o ṣe òpe ki o yà si ihin: fun ẹniti oye kù fun, o wipe, 5 Wá, jẹ ninu onjẹ mi, ki o si mu ninu ọti-waini mi ti mo dàlu. 6 Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye. 7 Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀. 8 Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ. 9 Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ. 10 Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye. 11 Nitori nipasẹ mi li ọjọ rẹ yio ma lé si i, ati ọdun ìye rẹ yio si ma lé si i. 12 Bi iwọ ba gbọ́n, iwọ o gbọ́n fun ara rẹ: ṣugbọn bi iwọ ba iṣe ẹlẹgàn, iwọ nikan ni yio rù u. 13 Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan. 14 O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu. 15 Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe, 16 Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe, 17 Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn. 18 Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi.

Owe 10

Àwọn Owe Solomoni

1 OWE Solomoni ni wọnyi. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe inu-didùn baba rẹ̀, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rẹ̀. 2 Iṣura ìwa-buburu kò li ère: ṣugbọn ododo ni igbani kuro lọwọ ikú. 3 Oluwa kì yio jẹ ki ebi ki o pa ọkàn olododo; ṣugbọn o yi ifẹ awọn enia buburu danu. 4 Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá. 5 Ẹniti o ba kojọ ni igba-ẹ̀run li ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ba nsùn ni igba ikore li ọmọ ti idoju tì ni. 6 Ibukún wà li ori olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. 7 Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà. 8 Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun. 9 Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀. 10 Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun. 11 Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. 12 Irira ni irú ìja soke: ṣugbọn ifẹ bò gbogbo ẹ̀ṣẹ mọlẹ. 13 Li ète ẹniti o moye li a ri ọgbọ́n: ṣugbọn kùmọ ni fun ẹhin ẹniti oye kù fun. 14 Awọn ọlọgbọ́n a ma to ìmọ jọ: ṣugbọn ẹnu awọn aṣiwere sunmọ iparun. 15 Ọrọ̀ ọlọlà ni agbára rẹ̀: aini awọn talaka ni iparun wọn. 16 Iṣẹ olododo tẹ̀ si ìye; èro awọn enia buburu si ẹ̀ṣẹ. 17 Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna. 18 Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni. 19 Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n. 20 Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori. 21 Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n. 22 Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀. 23 Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye. 24 Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u. 25 Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun. 26 Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ. 27 Ibẹ̀ru Oluwa mu ọjọ gùn: ṣugbọn ọdun enia buburu li a o ṣẹ́ kuru. 28 Abá olododo ayọ̀ ni yio jasi: ṣugbọn ireti enia buburu ni yio ṣegbe. 29 Ọ̀na Oluwa jẹ́ ãbò fun ẹni iduroṣinṣin, ṣugbọn egbe ni fun awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. 30 A kì yio ṣi olododo ni ipo lai; ṣugbọn enia buburu kì yio gbe ilẹ̀-aiye. 31 Ẹnu olõtọ mu ọgbọ́n jade; ṣugbọn ahọn arekereke li a o ke kuro. 32 Ete olododo mọ̀ ohun itẹwọgba; ṣugbọn ẹnu enia buburu nsọ̀rọ arekereke.

Owe 11

1 OṢUWỌN eke irira ni loju Oluwa; ṣugbọn òṣuwọn otitọ ni didùn inu rẹ̀. 2 Bi igberaga ba de, nigbana ni itiju de, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu onirẹlẹ. 3 Otitọ aduro-ṣinṣin ni yio ma tọ́ wọn; ṣugbọn arekereke awọn olurekọja ni yio pa wọn run. 4 Ọrọ̀ kì ini anfani li ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo ni igbani lọwọ ikú. 5 Ododo ẹni-pipé yio ma tọ́ ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu ninu ìwa-buburu rẹ̀. 6 Ododo awọn aduro-ṣinṣin yio gbà wọn là: ṣugbọn awọn olurekọja li a o mu ninu iṣekuṣe wọn: 7 Nigbati enia buburu ba kú, ireti rẹ̀ a dasan, ireti awọn alaiṣedede enia a si dasan. 8 A yọ olododo kuro ninu iyọnu, enia buburu a si bọ si ipò rẹ̀. 9 Ẹnu li agabagebe ifi pa aladugbo rẹ̀: ṣugbọn ìmọ li a o fi gbà awọn olododo silẹ. 10 Nigbati o ba nṣe rere fun olododo, ilu a yọ̀: nigbati enia buburu ba ṣegbe, igbe-ayọ̀ a ta. 11 Nipa ibukún aduro-ṣinṣin ilu a gbé lèke: ṣugbọn a bì i ṣubu nipa ẹnu enia buburu. 12 Ẹniti oye kù fun gàn ọmọnikeji rẹ̀; ṣugbọn ẹni oye a pa ẹnu rẹ̀ mọ́. 13 Ẹniti nṣofofo fi ọ̀ran ipamọ́ hàn; ṣugbọn ẹniti nṣe olõtọ-ọkàn a pa ọ̀rọ na mọ́. 14 Nibiti ìgbimọ kò si, awọn enia a ṣubu; ṣugbọn ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni ailewu. 15 Ẹniti o ba ṣe onigbọwọ fun alejo, ni yio ri iyọnu; ẹniti o ba si korira iṣegbọwọ wà lailewu. 16 Obinrin olore-ọfẹ gbà iyìn: bi alagbara enia ti igbà ọrọ̀. 17 Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu. 18 Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun. 19 Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀. 20 Awọn ti iṣe alarekereke aiya, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn inu rẹ̀ dùn si awọn aduroṣinṣin: 21 Bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu kì yio lọ laijiya, ṣugbọn iru-ọmọ olododo li a o gbàla. 22 Bi oruka wura ni imu ẹlẹdẹ bẹ̃ni arẹwà obinrin ti kò moye. 23 Kiki rere ni ifẹ inu awọn olododo; ṣugbọn ibinu ni ireti awọn enia buburu. 24 Ẹnikan wà ti ntuka, sibẹ o mbi si i, ẹnikan si wà ti nhawọ jù bi o ti yẹ lọ, ṣugbọn kiki si aini ni. 25 Ọkàn iṣore li a o mu sànra; ẹniti o mbomirin ni, ontikararẹ̀ li a o si bomirin pẹlu. 26 Ẹniti o ba dawọ ọkà duro, on li enia o fibu: ṣugbọn ibukún yio wà li ori ẹniti o tà a. 27 Ẹniti o fi ara balẹ wá rere, a ri oju-rere: ṣugbọn ẹniti o nwá ibi kiri, o mbọ̀wá ba a. 28 Ẹniti o ba gbẹkẹle ọrọ̀ rẹ̀ yio ṣubu: ṣugbọn olododo yio ma gbà bi ẹka igi. 29 Ẹniti o ba yọ ile ara rẹ̀ li ẹnu yio jogun ofo: aṣiwere ni yio ma ṣe iranṣẹ fun ọlọgbọ́n aiya. 30 Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni. 31 Kiye si i a o san a fun olododo li aiye: melomelo li enia buburu ati ẹ̀lẹṣẹ.

Owe 12

1 ẸNIKẸNI ti o fẹ ẹkọ́, o fẹ ìmọ: ṣugbọn ẹniti o korira ibawi, ẹranko ni. 2 Enia rere ni ojurere lọdọ Oluwa: ṣugbọn enia ete buburu ni yio dalẹbi. 3 A kì yio fi ẹsẹ enia mulẹ nipa ìwa-buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo kì yio fatu. 4 Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rẹ̀: ṣugbọn eyi ti ndojuti ni dabi ọyún ninu egungun rẹ̀. 5 Ìro olododo tọ́: ṣugbọn ìgbimọ awọn enia buburu, ẹ̀tan ni. 6 Ọ̀rọ enia buburu ni lati luba fun ẹ̀jẹ: ṣugbọn ẹnu aduro-ṣinsin ni yio gbà wọn silẹ. 7 A bì enia buburu ṣubu, nwọn kò si si: ṣugbọn ile olododo ni yio duro. 8 A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn. 9 Ẹniti a ngàn, ti o si ni ọmọ-ọdọ, o san jù ẹ̀niti nyìn ara rẹ̀ ti kò si ni onjẹ. 10 Olododo enia mọ̀ ãjo ẹmi ẹran rẹ̀: ṣugbọn iyọ́nu awọn enia buburu, ìka ni. 11 Ẹniti o ro ilẹ rẹ̀ li a o fi onjẹ tẹlọrun: ṣugbọn ẹniti ntọ̀ enia-lasan lẹhin ni oye kù fun. 12 Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso. 13 Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju. 14 Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u. 15 Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n. 16 Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ. 17 Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan. 18 Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni. 19 Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni. 20 Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni. 21 Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi. 22 Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀. 23 Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere. 24 Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn. 25 Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀. 26 Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ. 27 Ọlẹ enia kò mu ohun ọdẹ rẹ̀; ṣugbọn lati jẹ alãpọn enia, ọrọ̀ iyebiye ni. 28 Li ọ̀na olododo ni ìye; ikú kò si loju ọ̀na otitọ.

Owe 13

1 ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi. 2 Enia yio jẹ rere nipa ère ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ifẹ ọkàn awọn olurekọja ni ìwa-agbara. 3 Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun. 4 Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra. 5 Olododo korira ẹ̀tan; ṣugbọn enia buburu mu ni hu ìwa irira on itiju. 6 Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ. 7 Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ. 8 Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi. 9 Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa. 10 Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà. 11 Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i. 12 Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni. 13 Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun. 14 Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú. 15 Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro. 16 Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ. 17 Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá. 18 Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun. 19 Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi. 20 Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe. 21 Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a. 22 Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo, 23 Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ; 24 Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a. 25 Olododo jẹ to itẹrun ọkàn rẹ̀; ṣugbọn inu awọn enia buburu ni yio ṣe alaini.

Owe 14

1 ỌLUKULUKU ọlọgbọ́n obinrin ni kọ́ ile rẹ̀: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ ara rẹ̀ fà a lulẹ. 2 Ẹniti o nrìn ni iduroṣiṣin rẹ̀ o bẹ̀ru Oluwa: ṣugbọn ẹniti o ṣe arekereke li ọ̀na rẹ̀, o gàn a. 3 Li ẹnu aṣiwere ni paṣan igberaga; ṣugbọn ète awọn ọlọgbọ́n ni yio pa wọn mọ́. 4 Nibiti malu kò si, ibujẹ a di ofo: ṣugbọn ibisi pupọ mbẹ nipa agbara malu. 5 Ẹlẹri olõtọ kò jẹ ṣeke: ṣugbọn ẹ̀tan li ẹlẹri eke ima sọ jade. 6 Ẹlẹgan nwá ọgbọ́n, kò si ri i: ṣugbọn ìmọ kò ṣoro fun ẹniti oye ye. 7 Kuro niwaju aṣiwere, ati lọdọ ẹniti kò ni ète ìmọ. 8 Ọgbọ́n amoye ni ati moye ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn iwere awọn aṣiwere li ẹ̀tan. 9 Aṣiwere nfi ẹbi-ẹ̀ṣẹ ṣẹsin: ṣugbọn ojurere wà larin awọn olododo. 10 Aiya mọ̀ ikoro ara rẹ̀; alejo kò si ni iṣe pẹlu ayọ̀ rẹ̀. 11 Ile enia buburu li a o run: ṣugbọn agọ ẹni diduroṣinṣin ni yio ma gbilẹ. 12 Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú. 13 Ninu ẹrín pẹlu, aiya a ma kãnu; ati li opin, ayọ̀ a di ibinujẹ. 14 Apadasẹhin li aiya ni itẹlọrun lati inu ọ̀na ara rẹ̀: ṣugbọn enia rere lati inu ohun ti iṣe tirẹ̀. 15 Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere. 16 Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju. 17 Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira. 18 Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade. 19 Awọn ẹni-buburu tẹriba niwaju awọn ẹnirere; ati awọn enia buburu li ẹnu-ọ̀na awọn olododo. 20 A tilẹ korira talaka lati ọdọ aladugbo rẹ̀ wá: ṣugbọn ọlọrọ̀ ni ọrẹ́ pupọ. 21 Ẹniti o kẹgàn ẹnikeji rẹ̀, o ṣẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba ṣãnu fun awọn talaka, ibukún ni fun u. 22 Awọn ti ngbìmọ buburu kò ha ṣina bi? ṣugbọn ãnu ati otitọ ni fun awọn ti ngbìmọ ire. 23 Ninu gbogbo lãla li ère pupọ wà: ṣugbọn ọ̀rọ-ẹnu, lasan ni. 24 Adé awọn ọlọgbọ́n li ọrọ̀ wọn: ṣugbọn iwère awọn aṣiwère ni wère. 25 Olõtọ ẹlẹri gbà ọkàn silẹ: ṣugbọn ẹlẹri ẹ̀tan sọ̀rọ eke. 26 Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀. 27 Ibẹ̀ru Oluwa li orisun ìye, lati kuro ninu ikẹkùn ikú. 28 Ninu ọ̀pọlọpọ enia li ọlá ọba: ṣugbọn ninu enia diẹ ni iparun ijoye. 29 Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke. 30 Ọkàn ti o yè kõro ni ìye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun. 31 Ẹniti o ba nni talaka lara, o gàn Ẹlẹda rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o ṣãnu fun talaka o bu ọlá fun u. 32 A pa enia buburu run ninu ìwa-buburu rẹ̀; ṣugbọn olododo ni ireti ninu ikú rẹ̀. 33 Ọgbọ́n fi idi kalẹ li aiya ẹniti o moye; ṣugbọn a fi i hàn laiya awọn aṣiwère. 34 Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn ẹ̀ṣẹ li ẹ̀gan orilẹ-ède. 35 Ojurere ọba mbẹ li ọdọ ọlọgbọ́n iranṣẹ; ṣugbọn ibinu rẹ̀ si iranṣẹ ti nhùwa itiju.

Owe 15

1 IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke. 2 Ahọn ọlọgbọ́n nlò ìmọ rere: ṣugbọn ẹnu aṣiwère a ma gufẹ wère. 3 Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere. 4 Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn. 5 Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye. 6 Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu. 7 Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃. 8 Ẹbọ awọn enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rẹ̀. 9 Ọ̀na enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn o fẹ ẹniti ntọ̀ ododo lẹhin. 10 Ikilọ kikan wà fun ẹniti o kọ̀ ọ̀na silẹ; ẹniti o ba si korira ibawi yio kú. 11 Ipo-okú ati iparun ṣi silẹ niwaju Oluwa; njẹ melomelo li aiya awọn ọmọ enia. 12 Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ. 13 Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi. 14 Aiya ẹniti oye ye nṣe afẹri ìmọ; ṣugbọn ẹnu aṣiwère nfi wère bọ́ ara rẹ̀. 15 Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo. 16 Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀. 17 Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀. 18 Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu. 19 Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni. 20 Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe ayọ̀ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rẹ̀. 21 Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin. 22 Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ. 23 Enia ni ayọ̀ nipa idahùn ẹnu rẹ̀; ati ọ̀rọ kan li akoko rẹ̀, o ti wọ̀ to? 24 Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ. 25 Oluwa yio run ile agberaga; ṣugbọn yio fi ìpãlà opó kalẹ. 26 Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀. 27 Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè. 28 Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade. 29 Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo. 30 Imọlẹ oju mu inu dùn; ihin rere si mu egungun sanra. 31 Ẹniti o ba gbọ́ ibawi ìye, a joko lãrin awọn ọlọgbọ́n. 32 Ẹniti o kọ̀ ẹkọ́, o gàn ọkàn ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba gbọ́ ibawi, o ni imoye. 33 Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.

Owe 16

1 IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn. 2 Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn. 3 Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ. 4 Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi. 5 Olukulùku enia ti o gberaga li aiya, irira ni loju Oluwa: bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, kì yio wà laijiya. 6 Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi. 7 Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia. 8 Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́. 9 Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀. 10 Ọrọ isọtẹlẹ mbẹ li ète ọba: ẹnu rẹ̀ kì iṣẹ̀ ni idajọ. 11 Iwọn ati òṣuwọn otitọ ni ti Oluwa: gbogbo okuta-ìwọn àpo, iṣẹ rẹ̀ ni. 12 Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li a ti fi idi itẹ́ kalẹ. 13 Ete ododo ni didùn-inu awọn ọba: nwọn si fẹ ẹniti nsọ̀rọ titọ. 14 Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u. 15 Ni imọlẹ oju ọba ni ìye; ojurere rẹ̀ si dabi awọsanma òjo arọkuro. 16 Lati ni ọgbọ́n, melomelo li o san jù wura lọ; ati lati ni oye, melomelo li o dara jù fadaka lọ. 17 Òpopo-ọ̀na awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi: ẹniti o pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́. 18 Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu. 19 O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun. 20 Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u. 21 Ọlọgbọ́n aiya li a o pè li amoye: didùn-ète a si ma mu ẹkọ́ pọ̀. 22 Oye li orisun ìye fun ẹniti o ni i: ṣugbọn ẹkọ́ aṣiwère ni iwère. 23 Aiya ọlọgbọ́n mu ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, o si mu ẹkọ́ pọ̀ li ète rẹ̀. 24 Ọrọ didùn dabi afara oyin, o dùn mọ ọkàn, o si ṣe ilera fun egungun. 25 Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú. 26 Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e. 27 Enia-buburu hù ìwa-ibi jade, ati li ète rẹ̀ bi ẹnipe iná jijo li o wà nibẹ. 28 Alayidayida enia dá ìja silẹ: asọ̀rọkẹlẹ yà awọn ọrẹ́ ni ipa. 29 Ẹni ìwa-agbara tàn aladugbo rẹ̀, a si mu u lọ si ipa-ọ̀na ti kò dara. 30 On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu. 31 Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo. 32 Ẹniti o lọra ati binu, o san jù alagbara lọ; ẹniti o si ṣe akoso ẹmi rẹ̀, o jù ẹniti o ṣẹgun ilu lọ. 33 A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.

Owe 17

1 OKELE gbigbẹ, ti on ti alafia, o san jù ile ti o kún fun ẹran-pipa ti on ti ìja. 2 Ọlọgbọ́n iranṣẹ yio ṣe olori ọmọ ti nhùwa itiju, yio si pin ogún lãrin awọn arakunrin. 3 Koro ni fun fadaka, ati ileru fun wura: bẹ̃li Oluwa ndan aiya wò. 4 Oluṣe buburu fetisi ète eke; ẹni-eké a si ma kiyesi ọ̀rọ ahọn buburu. 5 Ẹnikẹni ti o ba sín olupọnju jẹ, o gàn Ẹlẹda rẹ̀: ẹniti o ba si nyọ̀ si wahala kì yio wà li aijiya. 6 Ọmọ ọmọ li ade arugbo: ogo awọn ọmọ si ni baba wọn. 7 Ọ̀rọ daradara kò yẹ fun aṣiwère; bẹ̃li ète eke kò yẹ fun ọmọ-alade. 8 Okuta iyebiye jẹ ẹ̀bun li oju ẹniti o ni i; nibikibi ti o yi si, a ṣe rere. 9 Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa. 10 Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère. 11 Ẹni-ọ̀tẹ a ma wá kiki ibi kiri; nitorina iranṣẹ ìka li a o ran si i. 12 O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀. 13 Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀. 14 Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla. 15 Ẹniti o da enia buburu lare, ati ẹniti o da olododo lẹbi, ani awọn mejeji irira ni loju Oluwa. 16 Nitori kini iye owo yio ṣe wà lọwọ aṣiwère lati rà ọgbọ́n, sa wò o, kò ni oye? 17 Ọrẹ́ a ma fẹni nigbagbogbo, ṣugbọn arakunrin li a bi fun ìgba ipọnju. 18 Enia ti oye kù fun, a ṣe onigbọwọ, a si fi ara sọfà niwaju ọrẹ́ rẹ̀. 19 Ẹniti o fẹ ìja, o fẹ ẹ̀ṣẹ; ẹniti o kọ́ ẹnu-ọ̀na rẹ̀ ga, o nwá iparun. 20 Ẹniti o ni ayidayida ọkàn kì yio ri ire: ati ẹniti o ni ahọn ọ̀rọ-meji, a bọ sinu ibi. 21 Ẹniti o bi aṣiwère, o bi i si ibinujẹ rẹ̀; baba aṣiwère kò si li ayọ̀. 22 Inu-didùn mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ. 23 Enia buburu mu ẹ̀bun lati iṣẹpo-aṣọ lati yi ọ̀na idajọ pada. 24 Ọgbọ́n wà niwaju ẹniti o moye; ṣugbọn oju aṣiwère mbẹ li opin ilẹ̀-aiye. 25 Aṣiwère ọmọ ni ibinujẹ baba rẹ̀, ati kikoro ọkàn fun iya ti o bi i. 26 Pẹlupẹlu kò dara ki a ṣẹ́ olotitọ ni iṣẹ́, tabi ki a lu ọmọ-alade nitori iṣedẽde. 27 Ẹniti o ni ìmọ, a ṣẹ́ ọ̀rọ rẹ̀ kù: ọlọkàn tutu si li amoye enia. 28 Lõtọ, aṣiwère, nigbati o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́, a kà a si ọlọgbọ́n; ẹniti o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si li amoye.

Owe 18

1 ẸNITI o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀, yio si kọju ìja nla si ohunkohun ti iṣe ti oye. 2 Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn. 3 Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju. 4 Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn. 5 Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ. 6 Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá. 7 Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀. 8 Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ. 9 Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni. 10 Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là. 11 Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀. 12 Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ. 13 Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u. 14 Ọkàn enia yio faiyàrán ailera rẹ̀; ṣugbọn ọkàn ti o rẹ̀wẹsi, tani yio gbà a? 15 Aiya amoye ni ìmọ; eti ọlọgbọ́n a si ma ṣe afẹri ìmọ. 16 Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla. 17 Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ. 18 Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara. 19 Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin. 20 Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu. 21 Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀. 22 Ẹnikẹni ti o ri aya fẹ, o ri ohun rere, o si ri ojurere lọdọ Oluwa. 23 Talaka a ma bẹ̀ ẹ̀bẹ; ṣugbọn ọlọrọ̀ a ma fi ikanra dahùn. 24 Ẹniti o ni ọrẹ́ pupọ, o ṣe e si iparun ara rẹ̀; ọrẹ́ kan si mbẹ ti o fi ara mọni ju arakunrin lọ.

Owe 19

1 TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère. 2 Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu. 3 Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa. 4 Ọrọ̀ fà ọrẹ́ pupọ; ṣugbọn talaka di yiyà kuro lọdọ aladugbo rẹ̀. 5 Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ. 6 Ọpọlọpọ ni yio ma bẹ̀bẹ ojurere ọmọ-alade: olukuluku enia ni si iṣe ọrẹ́ ẹniti ntani li ọrẹ. 7 Gbogbo awọn arakunrin talaka ni ikorira rẹ̀: melomelo ni awọn ọrẹ́ rẹ̀ yio ha jina si i? o ntẹle ọ̀rọ wọn, ṣugbọn nwọn kò si. 8 Ẹniti o gbọ́n, o fẹ ọkàn ara rẹ̀: ẹniti o pa oye mọ́ yio ri rere. 9 Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ẹniti o si nṣeke yio ṣegbe. 10 Ohun rere kò yẹ fun aṣiwère; tabi melomelo fun iranṣẹ lati ṣe olori awọn ijoye. 11 Imoye enia mu u lọra ati binu; ogo rẹ̀ si ni lati ré ẹ̀ṣẹ kọja. 12 Ibinu ọba dabi igbe kiniun; ṣugbọn ọjurere rẹ̀ dabi ìri lara koriko. 13 Aṣiwère ọmọ ni ibanujẹ baba rẹ̀: ìja aya dabi ọ̀ṣọrọ òjo. 14 Ile ati ọrọ̀ li ogún awọn baba: ṣugbọn amoye aya, lati ọdọ Oluwa wá ni. 15 Imẹlẹ mu ni sun orun fọnfọn; ọkàn ọlẹ li ebi yio si pa. 16 Ẹniti o pa ofin mọ́, o pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ba kẹgàn ọ̀na rẹ̀ yio kú. 17 Ẹniti o ṣãnu fun talaka Oluwa li o win; ati iṣeun rẹ̀, yio san a pada fun u. 18 Nà ọmọ rẹ nigbati ireti wà, má si ṣe gbe ọkàn rẹ le ati pa a. 19 Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e. 20 Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ. 21 Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro. 22 Ẹwà enia ni iṣeun rẹ̀: talaka enia si san jù eleke lọ. 23 Ibẹ̀ru Oluwa tẹ̀ si ìye: ẹniti o ni i yio joko ni itẹlọrun; a kì yio fi ibi bẹ̀ ẹ wọ́. 24 Imẹlẹ enia kì ọwọ rẹ̀ sinu iṣasun, kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu ara rẹ̀. 25 Lu ẹlẹgàn, òpe yio si kiyesi ara: si ba ẹniti o moye wi, oye ìmọ yio si ye e. 26 Ẹniti o ba nṣìka si baba rẹ̀, ti o si le iya rẹ̀ jade, on li ọmọ ti nṣe itiju, ti o si mu ẹ̀gan wá. 27 Ọmọ mi, dẹkun ati fetisi ẹkọ́ ti imu ni ṣìna kuro ninu ọ̀rọ ìmọ. 28 Ẹlẹri buburu fi idajọ ṣẹsin: ẹnu enia buburu si gbe aiṣedẽde mì. 29 A pèse ọ̀rọ-idajọ fun awọn ẹlẹgàn, ati paṣan fun ẹ̀hin awọn aṣiwère.

Owe 20

1 ẸLẸYA li ọti-waini, alariwo li ọti lile, ẹnikẹni ti a ba fi tanjẹ kò gbọ́n. 2 Ibẹ̀ru ọba dabi igbe kiniun: ẹnikẹni ti o ba mu u binu, o ṣẹ̀ si ọkàn ara rẹ̀. 3 Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja: ṣugbọn olukuluku aṣiwère ni ima ja ìja nla. 4 Ọlẹ kò jẹ tu ilẹ nitori otutu; nitorina ni yio fi ma ṣagbe nigba ikore, kì yio si ni nkan. 5 Ìmọ ninu ọkàn enia dabi omi jijin; ṣugbọn amoye enia ni ifà a jade. 6 Ọ̀pọlọpọ enia ni ima fọnrere, olukuluku ọrẹ ara rẹ̀: ṣugbọn olõtọ enia tani yio ri i. 7 Olõtọ enia nrìn ninu iwa-titọ rẹ̀: ibukún si ni fun awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀! 8 Ọba ti o joko lori itẹ́ idajọ, o fi oju rẹ̀ fọ́n ìwa-ibi gbogbo ka. 9 Tali o le wipe, Mo ti mu aiya mi mọ́, emi ti mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi? 10 Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, bakanna ni mejeji ṣe irira loju Oluwa. 11 Iṣe ọmọde pãpa li a fi imọ̀ ọ, bi ìwa rẹ̀ ṣe rere ati titọ. 12 Eti igbọ́ ati oju irí, Oluwa li o ti dá awọn mejeji. 13 Máṣe fẹ orun sisùn, ki iwọ ki o má ba di talaka; ṣi oju rẹ, a o si fi onjẹ tẹ ọ lọrùn. 14 Kò ni lãri, kò ni lãri li oníbárà iwi; ṣugbọn nigbati o ba bọ si ọ̀na rẹ̀, nigbana ni iṣogo. 15 Wura wà ati iyùn ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn ète ìmọ, èlo iyebiye ni. 16 Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin. 17 Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún. 18 Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun. 19 Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire. 20 Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri. 21 Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀. 22 Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ. 23 Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, irira ni loju Oluwa; ìwọn irẹjẹ kò si dara. 24 Irin ti enia nrìn, lati ọdọ Oluwa ni; tani ninu awọn enia ti o le mọ̀ ọ̀na rẹ̀? 25 Idẹkùn ni fun enia lati yara ṣe ileri mimọ́, ati lẹhin ẹjẹ́, ki o ma ronu. 26 Ọlọgbọ́n ọba a tú enia buburu ka, a si mu ayika-kẹkẹ́ rẹ̀ kọja lori wọn. 27 Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma ṣe awari iyara inu. 28 Anu ati otitọ pa ọba mọ́: ãnu li a si fi ndi itẹ́ rẹ̀ mu. 29 Ogo awọn ọdọmọkunrin li agbara wọn: ẹwà awọn arugbo li ewú. 30 Apá ọgbẹ ni iwẹ̀ ibi nù kuro: bẹ̃ si ni ìna ti o wọ̀ odò ikùn lọ.

Owe 21

1 AIYA ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odò omi; on a si dari rẹ̀ si ìbikibi ti o wù u. 2 Gbogbo ọ̀na enia li o dara li oju ara rẹ̀: ṣugbọn Oluwa li o nṣe amọ̀na ọkàn. 3 Lati ṣe ododo ati idajọ, o ṣe itẹwọgba fun Oluwa jù ẹbọ lọ. 4 Gangan oju, ati igberaga aiya, ati itulẹ̀ enia buburu, ẹ̀ṣẹ ni. 5 Ìronu alãpọn si kiki ọ̀pọ ni; ṣugbọn ti olukuluku ẹniti o yara, si kiki aini ni. 6 Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri. 7 Iwa-agbara awọn enia buburu ni yio pa wọn run: nitori ti nwọn kọ̀ lati ṣe idajọ. 8 Ẹnikẹni ti o nrìn ọ̀na ayidayida, enia buburu ni; ṣugbọn oninu funfun ni iṣẹ rẹ̀ tọ́. 9 O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe. 10 Ọkàn enia buburu nwá ibi kiri: aladugbo rẹ̀ kò ri ojurere li oju rẹ̀. 11 Nigbati a ba jẹ ẹlẹgàn ni ìya, a sọ òpe di ọlọgbọ́n: nigbati a ba si nkọ́ ọlọgbọ́n, on o ma ni ìmọ. 12 Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun. 13 Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ̀ si igbe olupọnju, ontikararẹ̀ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbọ́. 14 Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile. 15 Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. 16 Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú. 17 Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀. 18 Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin. 19 O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ. 20 Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ. 21 Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá. 22 Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀. 23 Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu. 24 Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ. 25 Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe. 26 O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro. 27 Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀? 28 Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu. 29 Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀. 30 Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa. 31 A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.

Owe 22

1 ORUKỌ rere sàn ni yiyàn jù ọrọ̀ pupọ lọ, ati ojurere ifẹ jù fadaka ati wura lọ. 2 Ọlọrọ̀ ati talaka pejọ pọ̀: Oluwa li ẹlẹda gbogbo wọn. 3 Ọlọgbọ́n enia ti ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a si jẹ wọn niya. 4 Ere irẹlẹ ati ibẹ̀ru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati ìye. 5 Ẹgún ati idẹkùn mbẹ li ọ̀na alayidayida: ẹniti o ba pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yio jina si wọn. 6 Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀. 7 Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese. 8 Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan. 9 Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju. 10 Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun. 11 Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀. 12 Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po. 13 Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro. 14 Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀. 15 Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀. 16 Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.

Ọgbọ̀n Gbolohun tí Ọlọ́gbọ́n Sọ

17 Dẹti rẹ silẹ, ki o gbọ́ ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n, ki o si fi aiya rẹ si ẹkọ́ mi. 18 Nitori ohun didùn ni bi iwọ ba pa wọn mọ́ ni inu rẹ; nigbati a si pese wọn tan li ète rẹ. 19 Ki igbẹkẹle rẹ ki o le wà niti Oluwa, emi fi hàn ọ loni, ani fun ọ. 20 Emi kò ti kọwe ohun daradara si ọ ni igbimọ ati li ẹkọ́, 21 Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ? 22 Máṣe ja talaka li ole, nitori ti iṣe talaka: bẹ̃ni ki o má si ṣe ni olupọnju lara ni ibode: 23 Nitori Oluwa yio gbija wọn, yio si gbà ọkàn awọn ti ngbà lọwọ wọn. 24 Máṣe ba onibinu enia ṣe ọrẹ́; má si ṣe ba ọkunrin oninu-fùfu rìn. 25 Ki iwọ ki o má ba kọ́ ìwa rẹ̀, iwọ a si gbà ikẹkùn fun ara rẹ. 26 Máṣe wà ninu awọn ti nṣe igbọwọ, tabi ninu awọn ti o duro fun gbèse. 27 Bi iwọ kò ba ni nkan ti iwọ o fi san, nitori kini yio ṣe gbà ẹní rẹ kuro labẹ rẹ? 28 Máṣe yẹ̀ àla ilẹ igbàni, ti awọn baba rẹ ti pa. 29 Iwọ ri enia ti o nfi aiṣemẹlẹ ṣe iṣẹ rẹ̀? on o duro niwaju awọn ọba; on kì yio duro niwaju awọn enia lasan.

Owe 23

1 NIGBATI iwọ ba joko lati ba ijoye jẹun, kiyesi ẹniti o wà niwaju rẹ gidigidi. 2 Ki o si fi ọbẹ le ara rẹ li ọfun, bi iwọ ba iṣe okundùn enia. 3 Máṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀: nitoripe onjẹ ẹ̀tan ni. 4 Máṣe lãla ati lọrọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ. 5 Iwọ o ha fi oju rẹ wò o? kì yio si si mọ, nitoriti ọrọ̀ hu iyẹ-apá fun ara rẹ̀ bi ìdi ti nfò li oju ọrun. 6 Máṣe jẹ onjẹ oloju buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀. 7 Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ li o ri: mã jẹ, ki o si ma mu li o nwi fun ọ; ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò pẹlu rẹ. 8 Okele ti iwọ jẹ ni iwọ o pọ̀ jade, iwọ a si sọ ọ̀rọ didùn rẹ nù. 9 Máṣe sọ̀rọ li eti aṣiwère: nitoriti yio gàn ọgbọ́n ọ̀rọ rẹ. 10 Máṣe ṣi àla atijọ; má si ṣe bọ sinu oko alaini-baba. 11 Nitoripe Olurapada wọn lagbara; yio gbà ìja wọn ja ti awọn tirẹ. 12 Fi aiya si ẹkọ́, ati eti rẹ si ọ̀rọ ìmọ. 13 Máṣe fà ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde, nitoripe bi iwọ ba fi paṣan nà a, on kì yio kú. 14 Iwọ fi paṣan nà a, iwọ o si gbà ọkàn rẹ̀ la kuro li ọrun-apadi. 15 Ọmọ mi, bi ọkàn rẹ ba gbọ́n ọkàn mi yio yọ̀, ani emi pẹlu. 16 Inu mi yio si dùn nigbati ètè rẹ ba nsọ̀rọ titọ. 17 Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo. 18 Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro. 19 Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ. 20 Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ. 21 Nitoripe ọmuti ati ọjẹun ni yio di talaka; ọlẹ ni yio si fi akisa bò ara rẹ̀. 22 Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó. 23 Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye. 24 Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀. 25 Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn. 26 Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi. 27 Nitoripe agbere, iho jijin ni; ati ajeji obinrin, iho hiha ni. 28 On a si ba ni ibuba bi ole, a si sọ awọn olurekọja di pupọ ninu awọn enia. 29 Tali o ni òṣi? tali o ni ibinujẹ? tali o ni ijà? tali o ni asọ̀? tali o ni ọgbẹ lainidi, tali o ni oju pipọn. 30 Awọn ti o duro pẹ nibi ọti-waini; awọn ti nlọ idan ọti-waini àdalu wò. 31 Iwọ máṣe wò ọti-waini pe o pọn, nigbati o ba fi àwọ rẹ̀ han ninu ago, ti a ngbe e mì, ti o ndùn. 32 Nikẹhin on a buniṣán bi ejò, a si bunijẹ bi paramọlẹ. 33 Oju rẹ yio wò awọn ajeji obinrin, aiya rẹ yio si sọ̀rọ ayidayida. 34 Nitõtọ, iwọ o dabi ẹniti o dubulẹ li arin okun, tabi ẹniti o dubulẹ lòke òpó-ọkọ̀. 35 Iwọ o si wipe, nwọn lù mi; kò dùn mi; nwọn lù mi, emi kò si mọ̀: nigbawo li emi o ji? emi o tun ma wá a kiri.

Owe 24

1 IWỌ máṣe ilara si awọn enia buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ lati ba wọn gbe. 2 Nitoriti aiya wọn ngbiro iparun, ète wọn si nsọ̀rọ ìwa-ika. 3 Ọgbọ́n li a fi ikọ ile; oye li a si fi ifi idi rẹ̀ kalẹ. 4 Nipa ìmọ ni iyará fi ikún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati didùn. 5 Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ. 6 Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun. 7 Ọgbọ́n ga jù aṣiwère lọ: on kì yio yà ẹnu rẹ̀ ni ẹnu-bode. 8 Ẹniti nhùmọ ati ṣe ibi li a o pè li enia ìwa-ika. 9 Ironu wère li ẹ̀ṣẹ; irira ninu enia si li ẹlẹgàn. 10 Bi iwọ ba rẹwẹsi li ọjọ ipọnju, agbara rẹ ko to nkan. 11 Bi iwọ ba fà sẹhin ati gbà awọn ti a wọ́ lọ sinu ikú, ati awọn ti a yàn fun pipa. 12 Ti iwọ si wipe, wò o, awa kò mọ̀ ọ; kò ha jẹ pe ẹniti ndiwọ̀n ọkàn nkiyesi i? ati ẹniti npa ọkàn rẹ mọ́, on li o mọ̀, yio si san a fun enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. 13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nitoriti o dara; ati afara oyin, ti o dùn li ẹnu rẹ: 14 Bẹ̃ni ìmọ ọgbọ́n yio ri si ọkàn rẹ: bi iwọ ba ri i, nigbana ni ère yio wà, a kì yio si ke ireti rẹ kuro. 15 Máṣe ba ni ibuba bi enia buburu, lati gba ibujoko olododo: máṣe fi ibi isimi rẹ̀ ṣe ijẹ. 16 Nitoripe olõtọ a ṣubu nigba meje, a si tun dide: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu sinu ibi. 17 Máṣe yọ̀ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹ ki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsẹ̀: 18 Ki Oluwa ki o má ba ri i, ki o si buru li oju rẹ̀, on a si yi ibinu rẹ̀ pada kuro lori rẹ̀. 19 Máṣe ilara si awọn enia buburu, má si ṣe jowu enia buburu. 20 Nitoripe, ère kì yio si fun enia ibi; fitila enia buburu li a o pa. 21 Ọmọ mi, iwọ bẹ̀ru Oluwa ati ọba: ki iwọ ki o má si ṣe dàpọ mọ awọn ti nṣe ayidayida. 22 Nitoripe wàhala wọn yio dide lojiji, ati iparun awọn mejeji, tali o mọ̀ ọ!

Àfikún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Tẹ̀síwájú sí i

23 Wọnyi pẹlu ni ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n. Kò dara lati ṣe ojuṣãju ni idajọ. 24 Ẹniti o ba wi fun enia buburu pe, olododo ni iwọ; on ni awọn enia yio bú, awọn orilẹ-ède yio si korira rẹ̀. 25 Ṣugbọn awọn ti o ba a wi ni yio ni inu-didùn, ibukún rere yio si bọ̀ sori wọn. 26 Yio dabi ẹniti o ṣe ifẹnukonu: ẹniti o ba ṣe idahùn rere. 27 Mura iṣẹ rẹ silẹ lode, ki o si fi itara tulẹ li oko rẹ; nikẹhin eyi, ki o si kọ́ ile rẹ. 28 Máṣe ẹlẹri si ẹnikeji rẹ lainidi: ki iwọ ki o má si ṣe fi ète rẹ ṣẹ̀tan. 29 Máṣe wipe, bẹ̃li emi o ṣe si i, gẹgẹ bi o ti ṣe si mi: emi o san a fun ọkunrin na gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. 30 Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgbà-ajara ẹniti oye kù fun: 31 Si kiyesi i, ẹgún kún bo gbogbo rẹ̀, igbó si bo oju rẹ̀, iganna okuta rẹ̀ si wo lulẹ. 32 Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkàn mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gbà ẹkọ́. 33 Orun diẹ si i, õgbe diẹ, ikawọkòpọ lati sùn diẹ. 34 Bẹ̃li òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn; ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.

Owe 25

Àwọn Òwe Mìíràn tí Solomoni Pa

1 WỌNYI pẹlu li owe Solomoni, ti awọn ọkunrin Hesekiah, ọba Judah kọ silẹ. 2 Ogo Ọlọrun ni lati pa ọ̀ran mọ́: ṣugbọn ọlá awọn ọba ni lati wadi ọ̀ran. 3 Ọrun fun giga, ati ilẹ fun jijin bẹ̃ni a kò le iwadi aiya awọn ọba. 4 Mu idarọ kuro ninu fadaka, ohun-elo yio si jade fun alagbẹdẹ fadaka. 5 Mu enia buburu kuro niwaju ọba, a o si fi idi itẹ́ rẹ̀ kalẹ ninu ododo. 6 Máṣe ṣefefe niwaju ọba, má si ṣe duro ni ipò awọn enia nla. 7 Nitoripe, o san ki a wi fun ọ pe, wá soke nihin, jù ki a fà ọ tì sẹhin niwaju ọmọ-alade ti oju rẹ ti ri. 8 Máṣe jade lọ kankan lati jà, ki iwọ ki o má ba ṣe alaimọ̀ eyiti iwọ o ṣe li opin rẹ̀, nigbati aladugbo rẹ yio dojutì ọ. 9 Ba ẹnikeji rẹ ja ìja rẹ̀; ṣugbọn aṣiri ẹlomiran ni iwọ kò gbọdọ fihàn. 10 Ki ẹniti o ba gbọ́ ki o má ba dojuti ọ, ẹ̀gan rẹ kì yio si lọ kuro lai. 11 Bi eso igi wura ninu agbọ̀n fadaka, bẹ̃ni ọ̀rọ ti a sọ li akoko rẹ̀. 12 Bi oruka wura ati ohun ọṣọ́ wura daradara, bẹ̃li ọlọgbọ́n olubaniwi li eti igbọràn. 13 Bi otutu òjo-didì ni ìgba ikore, bẹ̃ni olõtọ ikọ̀ si awọn ti o rán a: nitoriti o tù awọn oluwa rẹ̀ ninu. 14 Ẹnikẹni ti o ba ṣefefe ninu ẹ̀bun ẹ̀tan, o dabi awọsanma ati afẹfẹ ti kò ni òjo. 15 Ipamọra pipẹ li a fi iyi ọmọ-alade li ọkàn pada, ahọn ti o kunna ni ifọ egungun. 16 Bi iwọ ba ri oyin, jẹ eyi ti o to fun ọ, ki o má ba su ọ, iwọ a si bì i. 17 Fà ẹṣẹ sẹhin kuro ni ile aladugbo rẹ; ki agara rẹ o má ba da a, on a si korira rẹ. 18 Ẹniti o jẹri eke si ẹnikeji rẹ̀, ni olugboro, ati idà, ati ọfà mimu. 19 Igbẹkẹle alaiṣõtọ enia ni ìgba ipọnju, o dabi ehin ti o ṣẹ́, ati ẹsẹ̀ ti o yẹ̀ lori ike. 20 Bi ẹniti o bọ aṣọ nigba otutu, ati bi ọti-kikan ninu ẽru, bẹ̃li ẹniti nkọrin fun ẹniti inu rẹ̀ bajẹ. 21 Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba si gbẹ ẹ, fun u li ohun mimu. 22 Nitoriti iwọ o kó ẹyin iná jọ si ori rẹ̀, Oluwa yio san fun ọ. 23 Afẹfẹ ariwa mu òjo wá, bẹ̃li ahọn isọ̀rọ-ẹni-lẹhin imu oju kikoro wá. 24 O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe. 25 Bi omi tutu si ọkàn ti ongbẹ ngbẹ, bẹ̃ni ihin-rere lati ilu okere wá. 26 Olododo ti o ṣipo pada niwaju enia buburu, o dabi orisun ti o wú, ati isun-omi ti o bajẹ. 27 Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni. 28 Ẹniti kò le ṣe akoso ara rẹ̀, o dabi ilu ti a wo lulẹ, ti kò si li odi.

Owe 26

1 BI òjo-didì ni ìgba ẹrun, ati bi òjo ni ìgba ikore, bẹ̃li ọlá kò yẹ fun aṣiwère. 2 Bi ẹiyẹ fun iṣikiri, ati alapandẹdẹ fun fifò, bẹ̃ni egún kì yio wá lainidi. 3 Lagbà fun ẹṣin, ijanu fun kẹtẹkẹtẹ, ati ọgọ fun ẹhin aṣiwère. 4 Máṣe da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki iwọ pãpa ki o má ba dabi rẹ̀. 5 Da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki on ki o má ba gbọ́n li oju ara rẹ̀. 6 Ẹniti o rán iṣẹ nipa ọwọ aṣiwère, o ke ẹsẹ ara rẹ̀ kuro, o si jẹ ara rẹ̀ niya. 7 Bi ẹsẹ mejeji ti rọ̀ silẹ lara amukun, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère. 8 Bi ẹniti o fi àpo okuta iyebiye sinu okiti okuta, bẹ̃li ẹniti nfi ọlá fun aṣiwère. 9 Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère. 10 Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo. 11 Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀. 12 Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ. 13 Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro. 14 Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀. 15 Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀. 16 Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran. 17 Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti. 18 Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú, 19 Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe? 20 Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da. 21 Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ. 22 Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ. 23 Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko. 24 Ẹniti o ba korira, ti o fi ète rẹ̀ ṣe agabagebe, yio si pa ẹ̀tan mọ́ ninu rẹ̀. 25 Nigbati o ba sọ̀rọ daradara, máṣe gbà a gbọ́: nitoripe irira meje li o wà li aiya rẹ̀, 26 Ẹniti a fi ẹ̀tan bò irira rẹ̀ mọlẹ, ìwa-buburu rẹ̀ li a o fi hàn niwaju gbogbo ijọ: 27 Ẹnikẹni ti o ba wà ihò yio ṣubu sinu rẹ̀: ẹniti o ba si nyi okuta, on ni yio pada tọ̀. 28 Ahọn eke korira awọn ti a fi njẹniya; ẹnu ipọnni a si ma ṣiṣẹ iparun.

Owe 27

1 MÁṢE leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ̀ ohun ti ọjọ kan yio hù jade. 2 Jẹ ki ẹlomiran ki o yìn ọ, ki o máṣe ẹnu ara rẹ; alejo, ki o má si ṣe ète ara rẹ. 3 Okuta wuwo, yanrin si wuwo, ṣugbọn ibinu aṣiwère, o wuwo jù mejeji lọ. 4 Ibinu ni ìka, irunu si ni kikún-omi; ṣugbọn tani yio duro niwaju owú. 5 Ibawi nigbangba, o san jù ifẹ ti o farasin lọ. 6 Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́: ṣugbọn ifẹnukonu ọta li ẹ̀tan. 7 Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin; ṣugbọn ọkàn ti ebi npa, ohun kikoro gbogbo li o dùn. 8 Bi ẹiyẹ ti ima fò kiri lati inu itẹ́ rẹ̀, bẹ̃li enia ti o nrìn kiri jina si ipò rẹ̀. 9 Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa. 10 Ọrẹ́ rẹ ati ọrẹ́ baba rẹ, máṣe kọ̀ silẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe lọ si ile arakunrin li ọjọ idãmu rẹ: nitoripe aladugbo ti o sunmọ ni, o san jù arakunrin ti o jina rere lọ. 11 Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn. 12 Amoye enia ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn awọn òpe kọja a si jẹ wọn niya. 13 Gbà aṣọ rẹ̀ nitoriti o ṣe onigbọwọ alejo, si gbà ohun ẹri lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin. 14 Ẹniti o ba ndide ni kutukutu ti o nfi ohùn rara kí ọrẹ́ rẹ̀, egún li a o kà a si fun u. 15 Ọṣọrọ-òjo li ọjọ òjo, ati onija obinrin, bakanna ni. 16 Ẹnikẹni ti o pa a mọ́, o pa ẹfũfu mọ́, ororo ọwọ-ọtún rẹ̀ yio si fihàn. 17 Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀. 18 Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun. 19 Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia. 20 Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia. 21 Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀. 22 Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ. 23 Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ. 24 Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran? 25 Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀. 26 Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye-owo oko. 27 Iwọ o si ni wàra ewurẹ to fun onjẹ rẹ, fun onjẹ awọn ara ile rẹ, ati fun onjẹ awọn iranṣẹ-birin rẹ.

Owe 28

1 ENIA buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun. 2 Nipa irekọja ilẹ li awọn ijoye idi pupọ, ṣugbọn nipa amoye ati oni ìmọ̀ enia kan, li a mu ilẹ pẹ. 3 Olupọnju ti o nni olupọnju lara, o dabi agbalọ òjo ti kò fi onjẹ silẹ. 4 Awọn ti o kọ̀ ofin silẹ a ma yìn enia buburu: ṣugbọn awọn ti o pa ofin mọ́ a ma binu si wọn. 5 Oye idajọ kò ye enia buburu: ṣugbọn awọn ti nṣe afẹri Oluwa moye ohun gbogbo. 6 Talaka ti nrin ninu iduro-ṣinṣin rẹ̀, o san jù alarekereke ìwa, bi o tilẹ ṣe ọlọrọ̀. 7 Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́, o ṣe ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ṣe ẹlẹgbẹ jẹguduragudu, o dojuti baba rẹ̀. 8 Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka. 9 Ẹniti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ pãpa yio di irira. 10 Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere. 11 Ọlọrọ̀ gbọ́n li oju ara rẹ̀: ṣugbọn talaka ti o moye ridi rẹ̀. 12 Nigbati awọn olododo enia ba nyọ̀, ọṣọ́ nla a wà; ṣugbọn nigbati enia buburu ba dide, enia a sá pamọ́. 13 Ẹniti o bo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọlẹ kì yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ̀ ọ silẹ yio ri ãnu. 14 Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru nigbagbogbo: ṣugbọn ẹniti o ba sé aiya rẹ̀ le ni yio ṣubu sinu ibi. 15 Bi kiniun ti nke ramùramu, ati ẹranko beari ti nfi ebi sare kiri; bẹ̃ni ẹni buburu ti o joye lori awọn talaka. 16 Ọmọ-alade ti o ṣe alaimoye pupọ ni iṣe ìwa-ika pupọ pẹlu: ṣugbọn eyiti o korira ojukokoro yio mu ọjọ rẹ̀ pẹ. 17 Enia ti o ba hù ìwa-ika si ẹ̀jẹ ẹnikeji, yio sá lọ si ihò: ki ẹnikan ki o máṣe mu u. 18 Ẹnikẹni ti o ba nrin dẽde ni yio là: ṣugbọn ẹniti o nfi ayidayida rìn loju ọ̀na meji, yio ṣubu ninu ọkan ninu wọn. 19 Ẹniti o ba ro ilẹ rẹ̀ yio li ọ̀pọ onjẹ: ṣugbọn ẹniti o ba ntọ̀ enia asan lẹhin yio ni òṣi to. 20 Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya. 21 Iṣojuṣãju enia kò dara: nitoripe fun òkele onjẹ kan, ọkunrin na yio ṣẹ̀. 22 Ẹniti o kanju ati là, o li oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀wá ta on. 23 Ẹniti o ba enia wi yio ri ojurere ni ikẹhin jù ẹniti nfi ahọn pọn ọ lọ. 24 Ẹnikẹni ti o ba nja baba tabi iya rẹ̀ li ole, ti o si wipe, kì iṣe ẹ̀ṣẹ; on na li ẹgbẹ apanirun. 25 Ẹniti o ṣe agberaga li aiya, a rú ìja soke, ṣugbọn ẹniti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o mu sanra. 26 Ẹniti o gbẹkẹ le aiya ara rẹ̀, aṣiwère ni; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nfi ọgbọ́n rìn, on li a o gbà la. 27 Ẹniti o ba nfi fun olupọnju kì yio ṣe alaini: ṣugbọn ẹniti o mu oju rẹ̀ kuro, yio gbà egún pupọ. 28 Nigbati enia buburu ba hù, awọn enia a sá pamọ́: ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣegbe, awọn olododo a ma pọ̀ si i.

Owe 29

1 ẸNITI a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe. 2 Nigbati awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ̀; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn. 3 Ẹnikẹni ti o fẹ ọgbọ́n, a mu baba rẹ̀ yọ̀: ṣugbọn ẹniti o mba panṣaga kẹgbẹ, a ba ọrọ̀ rẹ̀ jẹ. 4 Nipa idajọ li ọba imu ilẹ tòro: ṣugbọn ẹniti o ba ngbà ọrẹ a bì i ṣubu. 5 Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀. 6 Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀. 7 Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o. 8 Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro. 9 Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si. 10 Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀. 11 Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin. 12 Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru. 13 Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji. 14 Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai. 15 Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀. 16 Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn. 17 Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn. 18 Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́. 19 A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn. 20 Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ. 21 Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀. 22 Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja. 23 Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá. 24 Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan. 25 Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke. 26 Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá. 27 Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo: ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọ̀na, irira ni si enia buburu.

Owe 30

Àwọn Ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ

1 Ọ̀RỌ Aguri, ọmọ Jake, ọ̀rọ ẹkọ́ ti ọkunrin na ti sọ, fun Itieli, ani fun Itieli ati Ukali. 2 Nitõtọ emi ṣiwère jù ẹlomiran lọ, emi kò si ni imoye enia. 3 Emi kò tilẹ kọ́ ọgbọ́n, emi kò tilẹ ni ìmọ ohun mimọ́. 4 Tali o ti gòke lọ si ọrun, tabi ti o si sọkalẹ wá? tali o kó afẹfẹ jọ li ọwọ rẹ̀? tali o di omi sinu aṣọ; tali o fi gbogbo opin aiye le ilẹ? Orukọ rẹ̀ ti ijẹ, ati orukọ ọmọ rẹ̀ ti ijẹ, bi iwọ ba le mọ̀ ọ? 5 Gbogbo ọ̀rọ Oluwa jẹ́ otitọ: on li asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e. 6 Iwọ máṣe fi kún ọ̀rọ rẹ̀, ki on má ba ba ọ wi, a si mu ọ li eke.

Àwọn Òwe Mìíràn

7 Ohun meji ni mo tọrọ lọdọ rẹ; máṣe fi wọn dù mi ki emi to kú. 8 Mu asan ati eke jìna si mi: máṣe fun mi li òṣi, máṣe fun mi li ọrọ̀; fi onjẹ ti o to fun mi bọ mi. 9 Ki emi ki o má ba yó jù, ki emi ki o má si sẹ́ ọ, pe ta li Oluwa? tabi ki emi má ba tòṣi, ki emi si jale, ki emi si ṣẹ̀ si orukọ Ọlọrun mi. 10 Máṣe fi iranṣẹ sùn oluwa rẹ̀, ki o má ba fi ọ bu, ki iwọ má ba jẹbi. 11 Iran kan wà ti nfi baba rẹ̀ bu, ti kò si sure fun iya rẹ̀. 12 Iran kan wà, ti o mọ́ li oju ara rẹ̀, ṣugbọn a kò ti iwẹ̀ ẹ nù kuro ninu ẽri rẹ̀. 13 Iran kan wà, yẽ, oju rẹ̀ ti gbega to! ipenpeju rẹ̀ si gbé soke. 14 Iran kan wà, ehin ẹniti o dabi idà, erigi rẹ̀ dabi ọbẹ, lati jẹ talaka run kuro lori ilẹ, ati awọn alaini kuro ninu awọn enia. 15 Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to. 16 Isa-okú, ati inu àgan; ilẹ ti kì ikún fun omi; ati iná ti kì iwipe, o to. 17 Oju ti o sin baba rẹ̀ jẹ, ti o gàn ati gbọ́ ti iya rẹ̀, kanakáná ẹba odò ni yio yọ ọ jade, ọmọ idì a si mu u jẹ. 18 Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀. 19 Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia. 20 Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan. 21 Nitori ohun mẹta, aiye a di rũru, ati labẹ mẹrin ni kò le duro. 22 Iranṣẹ, nigbati o jọba; ati aṣiwère, nigbati o yo fun onjẹ; 23 Fun obinrin, ti a korira, nigbati a sọ ọ di iyale; ati fun iranṣẹbinrin, nigbati o di arole iya rẹ̀. 24 Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́. 25 Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run. 26 Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta. 27 Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́; 28 Ọmọle fi ọwọ rẹ̀ dì mu, o si wà li ãfin awọn ọba. 29 Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn: 30 Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan; 31 Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀. 32 Bi iwọ ba ti ṣiwère ni gbigbe ara rẹ soke, tabi bi iwọ ba ti ronú ibi, fi ọwọ rẹ le ẹnu rẹ. 33 Nitõtọ, mimì wàra ni imu orí-àmọ́ wá, ati fifun imu ni imu ẹ̀jẹ jade; bẹ̃ni riru ibinu soke ni imu ìja wá.

Owe 31

Ìmọ̀ràn fún Ọba

1 Ọ̀RỌ Lemueli, ọba, ọ̀rọ-ẹkọ́ ti ìya rẹ̀ kọ́ ọ. 2 Kini, ọmọ mi? ki si ni, ọmọ inu mi? ati kini, ọmọ ẹ̀jẹ́ mi? 3 Máṣe fi agbara rẹ fun awọn obinrin, tabi ìwa rẹ fun awọn obinrin ti mbà awọn ọba jẹ. 4 Kì iṣe fun awọn ọba, Lemueli, kì iṣe fun awọn ọba lati mu ọti-waini; bẹ̃ni kì iṣe fun awọn ọmọ alade lati fẹ ọti lile: 5 Ki nwọn ki o má ba mu, nwọn a si gbagbe ofin, nwọn a si yi idajọ awọn olupọnju. 6 Fi ọti lile fun ẹniti o mura tan lati ṣegbe, ati ọti-waini fun awọn oninu bibajẹ. 7 Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́. 8 Yà ẹnu rẹ fun ayadi, ninu ọ̀ran gbogbo ẹniti iṣe ọmọ iparun. 9 Yà ẹnu rẹ, fi ododo ṣe idajọ, ki o si gbèja talaka ati alaini.

Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere

10 Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn. 11 Aiya ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹ̀ru, bẹ̃ni on kì yio ṣe alaini ère iṣẹ. 12 Rere li obinrin na yio ma ṣe fun u, kì iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. 13 Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu. 14 O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá. 15 On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀. 16 O kiyesi oko, o si mu u: ère ọwọ rẹ̀ li o fi gbin ọgbà-ajara. 17 O fi agbara gbá ẹ̀gbẹ rẹ̀ li ọjá, o si mu apa rẹ̀ mejeji le. 18 O kiyesi i pe ọjà on dara: fitila rẹ̀ kò kú li oru. 19 O fi ọwọ rẹ̀ le kẹkẹ́-owú, ọwọ rẹ̀ si di ìranwu mu. 20 O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini. 21 On kò si bẹ̀ru òjo-didì fun awọn ara ile rẹ̀; nitoripe gbogbo awọn ara ile rẹ̀ li a wọ̀ li aṣọ iṣẹpo meji. 22 On si wun aṣọ titẹ́ fun ara rẹ̀; ẹ̀wu daradara ati elese aluko li aṣọ rẹ̀. 23 A mọ̀ ọkọ rẹ̀ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na. 24 O da aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si tà a, pẹlupẹlu o fi ọjá amure fun oniṣòwo tà. 25 Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ. 26 O fi ọgbọ́n yà ẹnu rẹ̀; ati li ahọn rẹ̀ li ofin iṣeun. 27 O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ. 28 Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u. 29 Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ. 30 Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun. 31 Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.

Oniwasu 1

Asán Ni Ilé Ayé

1 Ọ̀RỌ oniwasu, ọmọ Dafidi, ti o jọba ni Jerusalemu. 2 Asan inu asan, oniwasu na wipe, asan inu asan; gbogbo rẹ̀ asan ni! 3 Ere kili enia jẹ ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn? 4 Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai. 5 Õrun pẹlu là, õrun si wọ̀, o si yara lọ si ipò rẹ̀ nibiti o ti là. 6 Afẹfẹ nfẹ lọ siha gusu, a si yipada siha ariwa; o si nlọ sihin sọhun titi, afẹfẹ si tun pada gẹgẹ nipa ayika rẹ̀. 7 Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ. 8 Ọ̀rọ gbogbo kò to; enia kò le sọ ọ: iran kì isu oju, bẹ̃li eti kì ikún fun gbigbọ́. 9 Ohun ti o wà, on ni yio si wà; ati eyiti a ti ṣe li eyi ti a o ṣe; kò si ohun titun labẹ õrùn. 10 Ohun kan wà nipa eyi ti a wipe, Wò o, titun li eyi! o ti wà na nigba atijọ, ti o ti wà ṣaju wa. 11 Kò si iranti ohun iṣaju; bẹ̃ni iranti kì yio si fun ohun ikẹhin ti mbọ̀, lọdọ awọn ti mbọ̀ ni igba ikẹhin. 12 Emi oniwasu jọba lori Israeli ni Jerusalemu. 13 Mo si fi aiya mi si ati ṣe afẹri on ati wadi ọgbọ́n niti ohun gbogbo ti a nṣe labẹ ọrun, lãla kikan yi li Ọlorun fi fun awọn ọmọ enia lati ṣe lãla ninu rẹ̀. 14 Mo ti ri iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo. 15 Eyi ti o wọ́, a kò le mu u tọ́: ati iye àbuku, a kò le kà a. 16 Mo si ba aiya ara mi sọ̀rọ wipe, kiyesi i, mo li ọgbọ́n nla, mo si fi kún u jù gbogbo wọn lọ ti o ti ṣaju mi ni Jerusalemu; aiya mi si ri ohun pupọ nla niti ọgbọ́n ati ti ìmọ. 17 Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, ati lati mọ̀ isinwin ati iwère: nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi pẹlu jẹ imulẹmofo. 18 Nitoripe ninu ọgbọ́n pupọ ni ibinujẹ pupọ wà, ẹniti o si nsọ ìmọ di pupọ, o nsọ ikãnu di pupọ.

Oniwasu 2

1 EMI wi ninu mi pe, wá na! emi o fi iré-ayọ̀ dan ọ wò, nitorina mã jẹ afẹ! si kiyesi i, asan li eyi pẹlu! 2 Emi wi fun ẹrin pe, Iwère ni ọ: ati fun iré-ayọ̀ pe kili o nṣe? 3 Mo rò ninu aiya mi lati fi ọti-waini mu ara mi le, ṣugbọn emi nfi ọgbọ́n tọ́ aiya mi: on ati fi ọwọ le iwère, titi emi o fi ri ohun ti o dara fun ọmọ enia, ti nwọn iba mã ṣe labẹ ọrun ni iye ọjọ aiye wọn gbogbo. 4 Mo ṣe iṣẹ nla fun ara mi; mo kọ́ ile pupọ fun ara mi; mo gbin ọgbà-ajara fun ara mi. 5 Mo ṣe ọgbà ati agbala daradara fun ara mi, mo si gbin igi oniruru eso sinu wọn. 6 Mo ṣe adagun pupọ, lati ma bomi lati inu wọn si igbo ti o nmu igi jade wá: 7 Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi. 8 Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ. 9 Bẹ̃ni mo tobi, mo si pọ̀ si i jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju mi ni Jerusalemu: ọgbọ́n mi si mbẹ pẹlu mi. 10 Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi. 11 Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn. 12 Mo si yi ara mi pada lati wò ọgbọ́n, ati isinwin ati iwère: nitoripe kili ọkunrin na ti mbọ lẹhin ọba yio le ṣe? eyi ti a ti ṣe tan nigbani ni yio ṣe. 13 Nigbana ni mo ri pe ọgbọ́n ta wère yọ, to iwọn bi imọlẹ ti ta òkunkun yọ. 14 Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn. 15 Nigbana ni mo wi li aiya mi pe, Bi o ti nṣe si aṣiwère, bẹ̃li o si nṣe si emitikalami; nitori kili emi si ṣe gbọ́n jù? Nigbana ni mo wi li ọkàn mi pe, asan li eyi pẹlu. 16 Nitoripe iranti kò si fun ọlọgbọ́n pẹlu aṣiwère lailai; ki a wò o pe, bi akoko ti o kọja, bẹ̃li ọjọ ti mbọ, a o gbagbe gbogbo rẹ̀. Ọlọgbọ́n ha ṣe nkú bi aṣiwère? 17 Nitorina mo korira ìwa-laiye: nitoripe iṣẹ ti a ṣe labẹ õrun: ibi ni fun mi: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo. 18 Nitõtọ mo korira gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn: nitoriti emi o fi i silẹ fun enia ti mbọ̀ lẹhin mi. 19 Tali o si mọ̀ bi ọlọgbọ́n ni yio ṣe tabi aṣiwère? sibẹ on ni yio ṣe olori iṣẹ mi gbogbo ninu eyi ti mo ṣe lãla, ati ninu eyi ti mo fi ara mi hàn li ọlọgbọ́n labẹ õrùn. Asan li eyi pẹlu. 20 Nitorina mo kirilọ lati mu aiya mi ṣí kuro ninu gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn. 21 Nitoriti enia kan mbẹ, iṣẹ ẹniti o wà li ọgbọ́n ati ni ìmọ, ati ni iṣedẽde; sibẹ ẹniti kò ṣe lãla ninu rẹ̀ ni yio fi i silẹ fun ni ipin rẹ̀. Eyi pẹlu asan ni ati ibi nlanla. 22 Nitoripe kili enia ni ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o fi nṣe lãla labẹ õrùn? 23 Nitoripe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ikãnu ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ, nitõtọ aiya rẹ̀ kò simi li oru. Eyi pẹlu asan ni. 24 Kò si ohun ti o dara fun enia jù ki o jẹ, ki o si mu ati ki o mu ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere ninu lãla rẹ̀. Eyi ni mo ri pẹlu pe, lati ọwọ Ọlọrun wá ni. 25 Nitoripe tali o le jẹun, tabi tani pẹlu ti o le mọ̀ adùn jù mi lọ? 26 Nitoripe Ọlọrun fun enia ti o tọ li oju rẹ̀ li ọgbọ́n, ati ìmọ ati ayọ̀: ṣugbọn ẹlẹṣẹ li o fi ìṣẹ́ fun, lati ma kó jọ ati lati ma tò jọ ki on ki o le ma fi fun ẹni rere niwaju Ọlọrun. Eyi pẹlu asan ni ati imulẹmofo.

Oniwasu 3

1 OLUKULÙKU ohun li akoko wà fun, ati ìgba fun iṣẹ gbogbo labẹ ọrun. 2 Ìgba bibini, ati ìgba kikú, ìgba gbigbin ati ìgba kika ohun ti a gbin; 3 Ìgba pipa ati ìgba imularada; ìgba wiwo lulẹ ati ìgba kikọ; 4 Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo; 5 Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra; 6 Ìgba wiwari, ati ìgba sísọnu: ìgba pipamọ́ ati ìgba ṣiṣa tì; 7 Ìgba fifaya, ati ìgba rirán; ìgba didakẹ, ati ìgba fifọhùn; 8 Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia. 9 Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla? 10 Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀. 11 O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin. 12 Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀. 13 Ati pẹlu ki olukulùku enia ki o ma jẹ ki o si ma mu, ki o si ma jadùn gbogbo lãla rẹ̀, ẹ̀bun Ọlọrun ni. 14 Emi mọ̀ pe ohunkohun ti Ọlọrun ṣe yio wà lailai: a kò le fi ohun kan kún u, bẹ̃li a kò le mu ohun kan kuro ninu rẹ̀; Ọlọrun si ṣe eyi ki enia ki o le ma bẹ̀ru rẹ̀. 15 Ohun ti o ti wà ri mbẹ nisisiyi, ati eyi ti yio si wà, o ti wà na; Ọlọrun si bère eyi ti o ti kọja lọ. 16 Ati pẹlupẹlu mo ri ibi idajọ labẹ õrùn pe ìwa buburu mbẹ nibẹ; ati ni ibi ododo, pe aiṣedẽde mbẹ nibẹ. 17 Mo wi li aiya mi pe, Ọlọrun yio ṣe idajọ olododo ati enia buburu: nitoripe ìgba kan mbẹ fun ipinnu ati fun iṣẹ gbogbo. 18 Mo wi li aiya mi niti ìwa awọn ọmọ enia; ki Ọlọrun ki o le fi wọn hàn, ati ki nwọn ki o le ri pe ẹran ni awọn tikalawọn fun ara wọn. 19 Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀. 20 Nibikanna ni gbogbo wọn nlọ; lati inu erupẹ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn si tun pada di erupẹ. 21 Tali o mọ̀ ẹmi ọmọ enia ti ngoke si apa òke, ati ẹmi ẹran ti nsọkalẹ si isalẹ ilẹ? 22 Nitorina mo woye pe kò si ohun ti o dara jù ki enia ki o ma yọ̀ ni iṣẹ ara rẹ̀; nitori eyini ni ipin rẹ̀: nitoripe tani yio mu u wá ri ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀.

Oniwasu 4

1 BẸ̃NI mo pada, mo si rò inilara gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; mo si wò omije awọn ti a nnilara, nwọn kò si ni olutunu; ati lọwọ aninilara wọn ni ipá wà; ṣugbọn nwọn kò ni olutunu. 2 Nitorina mo yìn okú ti o ti kú pẹ jù awọn alãye ti o wà lãye sibẹ. 3 Nitõtọ, ẹniti kò ti isi san jù awọn mejeji; ẹniti kò ti iri iṣẹ buburu ti a nṣe labẹ õrùn. 4 Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo. 5 Aṣiwère fọwọ rẹ̀ lọwọ, o si njẹ ẹran-ara rẹ̀. 6 Onjẹ ikunwọ kan pẹlu idakẹjẹ, o san jù ikunwọ meji lọ ti o kun fun lãla ati imulẹmofo. 7 Nigbana ni mo pada, mo si ri asan labẹ õrun. 8 Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi. 9 Ẹni meji san jù ẹnikan; nitori nwọn ni ère rere fun lãla wọn. 10 Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide. 11 Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru? 12 Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja. 13 Otoṣi ipẹ̃rẹ ti o ṣe ọlọgbọ́n, o san jù arugbo ati aṣiwère ọba lọ ti kò mọ̀ bi a ti igbà ìmọran. 14 Nitoripe lati inu tubu li o ti jade wá ijọba; bi a tilẹ ti bi i ni talaka ni ijọba rẹ̀. 15 Mo ri gbogbo alãye ti nrìn labẹ õrun, pẹlu ipẹ̃rẹ ekeji ti yio dide duro ni ipò rẹ̀. 16 Kò si opin gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo awọn ti on wà ṣiwaju wọn: awọn pẹlu ti mbọ̀ lẹhin kì yio yọ̀ si i. Nitõtọ asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.

Oniwasu 5

1 PA ẹsẹ rẹ mọ́ nigbati iwọ ba nlọ si ile Ọlọrun, ki iwọ ki o si mura ati gbọ́ jù ati ṣe irubọ aṣiwère: nitoriti nwọn kò rò pe nwọn nṣe ibi. 2 Máṣe fi ẹnu rẹ yara, ki o má si jẹ ki aiya rẹ ki o yara sọ ọ̀rọ niwaju Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun mbẹ li ọrun, iwọ si mbẹ li aiye: nitorina jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o mọ̀ ni ìwọn. 3 Nitoripe nipa ọ̀pọlọpọ iṣẹ ni alá ti iwá; bẹ̃ni nipa ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ li ã mọ̀ ohùn aṣiwère. 4 Nigbati iwọ ba jẹ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjẹ́. 5 O san ki iwọ ki o má jẹ ẹjẹ́, jù ki iwọ ki o jẹ ẹjẹ́, ki o má san a. 6 Máṣe jẹ ki ẹnu rẹ ki o mu ara rẹ ṣẹ̀: ki iwọ ki o má si ṣe wi niwaju iranṣẹ Ọlọrun pe, èṣi li o ṣe: nitori kili Ọlọrun yio ṣe binu si ohùn rẹ, a si ba iṣẹ ọwọ rẹ jẹ? 7 Nitoripe bi ninu ọ̀pọlọpọ alá ni asan wà, bẹ̃ni ninu ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ pẹlu: ṣugbọn iwọ bẹ̀ru Ọlọrun. 8 Bi iwọ ba ri inilara awọn olupọnju, ati ifi agbara yi idajọ ati otitọ pada ni igberiko, máṣe jẹ ki ẹnu ki o yà ọ si ọ̀ran na: nitoripe ẹniti o ga jù nṣọ ẹniti o ga, ati ẹni-giga-julọ wà lori wọn. 9 Pẹlupẹlu ère ilẹ ni fun gbogbo enia: a si nsìn ọba tikalarẹ pãpa lati inu oko wa. 10 Ẹniti o ba fẹ fadaka, fadaka kì yio tẹ́ ẹ lọrun; bẹ̃li ẹniti o fẹ ọrọ̀ kì yio tẹ́ ẹ lọrun: asan li eyi pẹlu. 11 Nigbati ẹrù ba npọ̀ si i, awọn ti o si njẹ ẹ a ma pọ̀ si i: ore ki tilẹ ni fun ẹniti o ni i bikoṣepe ki nwọn ki o ma fi oju wọn wò o? 12 Didùn ni orun oniṣẹ, iba jẹ onjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọrọ̀ kì ijẹ, ki o sùn. 13 Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i. 14 Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀. 15 Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀. 16 Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ? 17 Li ọjọ rẹ̀ gbogbo pẹlu, o njẹun li òkunkun, o si ni ibinujẹ pupọ ati àrun ati irora rẹ̀. 18 Kiyesi eyi ti mo ri: o dara o si yẹ fun enia, ki o jẹ, ki o si mu, ki o si ma jẹ alafia ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn, ni iye ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, ti Ọlọrun fi fun u: nitori eyi ni ipin tirẹ̀. 19 Bi Ọlọrun ba fi ọrọ̀ fun ẹnikẹni, ti o si fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀: ati lati mu ipin rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu lãla rẹ eyi; pẹlu ẹ̀bun Ọlọrun ni. 20 Nitoriti kì yio ranti ọjọ aiye rẹ̀ pọju; nitoriti Ọlọrun da a lohùn ninu ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Oniwasu 6

1 IBI kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, o si ṣọpọ lãrin awọn ọmọ enia. 2 Ẹniti Ọlọrun fi ọrọ̀, ọlà ati ọlá fun, ti kò si si nkan ti o si kù fun ọkàn rẹ̀ ninu ohun gbogbo ti o fẹ, ṣugbọn ti Ọlọrun kò fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn awọn ajeji enia li o njẹ ẹ: asan li eyi, àrun buburu si ni. 3 Bi ọkunrin kan bi ọgọrun ọmọ, ti o si wà li ọdun pupọ, tobẹ̃ ti ọjọ ọdun rẹ̀ pọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò si kún fun ohun didara, ati pẹlu ti a kò si sinkú rẹ̀; mo ni, ọmọ iṣẹnu san jù u lọ. 4 Nitoripe lasan li o wá, o si lọ li òkunkun, òkunkun li a o si fi bo orukọ rẹ̀ mọlẹ. 5 Pẹlupẹlu on kò ri õrùn kò mọ ohun kan: eyi ni isimi jù ekeji lọ. 6 Ani bi o tilẹ wà ni ẹgbẹrun ọdun lẹrin-meji, ṣugbọn kò ri rere: ibikanna ki gbogbo wọn ha nrè? 7 Gbogbo lãla enia ni fun ẹnu rẹ̀, ṣugbọn a kò ti itẹ adùn ọkàn rẹ̀ lọrun. 8 Nitoripe ère kili ọlọgbọ́n ni jù aṣiwère lọ? kini talaka ni ti o mọ̀ bi a ti rin niwaju awọn alãye? 9 Eyiti oju ri san jù irokakiri ifẹ lọ; asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo. 10 Eyi ti o wà, a ti da orukọ rẹ̀ ri, a si ti mọ̀ ọ pe, enia ni: bẹ̃ni kò le ba ẹniti o lagbara jù u lọ jà. 11 Kiyesi i ohun pupọ li o wà ti nmu asan bi si i, ère kili enia ni? 12 Nitoripe tali o mọ̀ ohun ti o dara fun enia li aiye yi, ni iye ọjọ asan rẹ̀ ti nlọ bi ojiji? nitoripe tali o le sọ fun enia li ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀ labẹ õrùn?

Oniwasu 7

1 ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ. 2 O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀. 3 Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san. 4 Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré. 5 O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère. 6 Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu. 7 Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ. 8 Opin nkan san jù ipilẹṣẹ rẹ̀ lọ: ati onisuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga. 9 Máṣe yara li ọkàn rẹ lati binu, nitoripe ibinu simi li aiya aṣiwère. 10 Iwọ máṣe wipe, nitori kili ọjọ iṣaju ṣe san jù wọnyi lọ? nitoripe iwọ kò fi ọgbọ́n bere niti eyi. 11 Ọgbọ́n dara gẹgẹ bi iní, ati nipasẹ rẹ̀ ère wà fun awọn ti nri õrùn. 12 Nitoripe ãbò li ọgbọ́n, ani bi owo ti jẹ́ abò: ṣugbọn ère ìmọ ni pe, ọgbọ́n fi ìye fun awọn ti o ni i. 13 Wò iṣẹ Ọlọrun: nitoripe, tali o le mu eyini tọ́ ti on ṣe ni wiwọ? 14 Li ọjọ alafia, mã yọ̀, ṣugbọn li ọjọ ipọnju, ronu pe, bi Ọlọrun ti da ekini bẹ̃li o da ekeji, niti idi eyi pe ki enia ki o máṣe ri nkan ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀. 15 Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀. 16 Iwọ máṣe ododo aṣeleke; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fi ara rẹ ṣe ọlọgbọ́n aṣeleke: nitori kini iwọ o ṣe run ara rẹ? 17 Iwọ máṣe buburu aṣeleke, bẹ̃ni ki iwọ ki o má ṣiwère; nitori kini iwọ o ṣe kú ki ọjọ rẹ ki o to pe? 18 O dara ki iwọ ki o dì eyi mu; pẹlupẹlu iwọ máṣe yọ ọwọ rẹ kuro ninu eyi: nitori ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ni yio yọ kuro ninu rẹ̀ gbogbo. 19 Ọgbọ́n mu ọlọgbọ́n lara le jù enia alagbara mẹwa lọ ti o wà ni ilu. 20 Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ. 21 Pẹlupẹlu máṣe fiyesi gbogbo ọ̀rọ ti a nsọ; ki iwọ ki o má ba gbọ́ ki iranṣẹ rẹ ki o bu ọ. 22 Nitoripe nigba pupọ pẹlu li aiya rẹ mọ̀ pe iwọ tikalarẹ pẹlu ti bu awọn ẹlomiran. 23 Idi gbogbo wọnyi ni mo fi ọgbọ́n wá; mo ni, emi o gbọ́n: ṣugbọn ọ̀na rẹ̀ jin si mi. 24 Eyi ti o jinna, ti o si jinlẹ gidigidi, tali o le wá a ri? 25 Mo fi aiya mi si i lati mọ̀, on ati wadi, on ati ṣe afẹri ọgbọ́n ati oye, on ati mọ̀ ìwa buburu wère, ani ti wère ati ti isinwin: 26 Mo si ri ohun ti o korò jù ikú lọ, ani obinrin ti aiya rẹ̀ iṣe idẹkun ati àwọn, ati ọwọ rẹ̀ bi ọbára: ẹnikẹni ti inu Ọlọrun dùn si yio bọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹṣẹ li a o ti ọwọ rẹ̀ mu. 27 Kiyesi i, eyi ni mo ri, bẹ̃li oniwasu wi, ni wiwadi rẹ̀ li ọkọkan lati ri oye. 28 Ti ọkàn mi nwakiri sibẹ, ṣugbọn emi kò ri: ọkunrin kanṣoṣo ninu ẹgbẹrun ni mo ri; ṣugbọn obinrin kan ninu gbogbo awọn wọnni, emi kò ri. 29 Kiyesi i, eyi nikanṣoṣo ni mo ri, pe, Ọlọrun ti da enia ni iduroṣinṣin; ṣugbọn nwọn ti ṣe afẹri ihumọkihumọ.

Oniwasu 8

1 TALI o dabi ọlọgbọ́n enia? tali o si mọ̀ itumọ nkan? Ọgbọ́n enia mu oju rẹ̀ dán, ati igboju rẹ̀ li a o si yipada. 2 Mo ba ọ mọ̀ ọ pe, ki iwọ ki o pa ofin ọba mọ́, eyini si ni nitori ibura Ọlọrun. 3 Máṣe yara ati jade kuro niwaju rẹ̀: máṣe duro ninu ohun buburu; nitori ohun ti o wù u ni iṣe. 4 Nibiti ọ̀rọ ọba gbe wà, agbara mbẹ nibẹ; tali o si le wi fun u pe, kini iwọ nṣe nì? 5 Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́ kì yio mọ̀ ohun buburu: aiya ọlọgbọ́n enia si mọ̀ ìgba ati àṣa. 6 Nitoripe ohun gbogbo ti o wuni ni ìgba ati àṣa wà fun, nitorina òṣi enia pọ̀ si ori ara rẹ̀. 7 Nitoriti kò mọ̀ ohun ti mbọ̀: tali o si le wi fun u bi yio ti ri? 8 Kò si enia kan ti o lagbara lori ẹmi lati da ẹmi duro; bẹ̃ni kò si lagbara li ọjọ ikú: kò si iránpada ninu ogun na; bẹ̃ni ìwa buburu kò le gbà awọn oluwa rẹ̀. 9 Gbogbo nkan wọnyi ni mo ri, mo si fiyè si iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn: ìgba kan mbẹ ninu eyi ti ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀. 10 Bẹ̃ni mo si ri isinkú enia buburu, ati awọn ti o ṣe otitọ ti o wá ti o si lọ kuro ni ibi mimọ́, a si gbagbe wọn ni ilu na: asan li eyi pẹlu. 11 Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pãpa lati huwa ibi. 12 Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rẹ̀ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ̀ pe yio dara fun awọn ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o bẹ̀ru niwaju rẹ̀: 13 Ṣugbọn kì yio dara fun enia buburu, bẹ̃ni kì yio fa ọjọ rẹ̀ gun ti o dabi ojiji, nitoriti kò bẹ̀ru niwaju Ọlọrun. 14 Asan kan mbẹ ti a nṣe li aiye; niti pe, olõtọ enia wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ buburu; ati pẹlu, enia buburu wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ olododo: mo ni asan li eyi pẹlu. 15 Nigbana ni mo yìn iré, nitori enia kò ni ohun rere labẹ õrùn jù jijẹ ati mimu, ati ṣiṣe ariya: nitori eyini ni yio ba a duro ninu lãla rẹ̀ li ọjọ aiye rẹ̀, ti Ọlọrun fi fun u labẹ õrùn. 16 Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, on ati ri ohun ti a ṣe lori ilẹ: (ẹnikan sa wà pẹlu ti kò fi oju rẹ̀ ba orun li ọsan ati li oru.) 17 Nigbana ni mo wò gbogbo iṣẹ Ọlọrun, pe enia kò le ridi iṣẹ ti a nṣe labẹ õrùn: nitoripe bi enia tilẹ gbiyanju ati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio le ri i; ati pẹlupẹlu bi ọlọgbọ́n enia rò lati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio lè ridi rẹ̀.

Oniwasu 9

1 NITORI nkan yi ni mo rò li aiya mi, ani lati wadi gbogbo eyi pe, olododo, ati ọlọgbọ́n, ati iṣẹ wọn, lọwọ Ọlọrun li o wà: ifẹni ati irira, kò si ẹniti o mọ̀, gbogbo eyi wà niwaju wọn. 2 Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn: ohun kanna li o nṣe si olododo, ati si ẹni buburu; si enia rere, ati si mimọ́ ati si alaimọ́; si ẹniti nrubọ, ati si ẹniti kò rubọ: bi enia rere ti ri, bẹ̃ li ẹ̀lẹṣẹ; ati ẹniti mbura bi ẹniti o bẹ̀ru ibura. 3 Eyi ni ibi ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn, pe iṣẹ kanna ni si gbogbo wọn: ati pẹlu, aiya awọn ọmọ enia kún fun ibi, isinwin mbẹ ninu wọn nigbati wọn wà lãye, ati lẹhin eyini; nwọn a lọ sọdọ awọn okú. 4 Nitoripe tali ẹniti a yàn, ti ireti alãye wà fun: nitoripe ãye ajá san jù okú kiniun lọ. 5 Nitori alãye mọ̀ pe awọn o kú; ṣugbọn awọn okú kò mọ̀ ohun kan, bẹ̃ni nwọn kì ili ère mọ; nitori iranti wọn ti di igbagbe. 6 Ifẹ wọn pẹlu, ati irira wọn, ati ilara wọn, o parun nisisiyi; bẹ̃ni nwọn kò si ni ipin mọ lailai ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn. 7 Ma ba tirẹ lọ, ma fi ayọ̀ jẹ onjẹ rẹ, ki o si mã fi inu-didun mu ọti-waini rẹ: nitoripe Ọlọrun tẹwọgba iṣẹ rẹ nisisiyi. 8 Jẹ ki aṣọ rẹ ki o ma fún nigbagbogbo; ki o má si jẹ ki ori rẹ ki o ṣe alaini ororo ikunra, 9 Ma fi ayọ̀ ba aya rẹ gbe ti iwọ fẹ ni gbogbo ọjọ aiye asan rẹ, ti o fi fun ọ labẹ õrùn ni gbogbo ọjọ asan rẹ: nitori eyini ni ipin tirẹ li aiye yi, ati ninu lãla ti iwọ ṣe labẹ õrùn. 10 Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè. 11 Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn. 12 Nitoripe enia pẹlu kò mọ̀ ìgba tirẹ̀; bi ẹja ti a mu ninu àwọn buburu, ati bi ẹiyẹ ti a mu ninu okùn; bẹ̃li a ndẹ awọn ọmọ enia ni ìgba buburu, nigbati o ṣubu lù wọn lojiji. 13 Ọgbọ́n yi ni mo ri pẹlu labẹ õrùn, o si dabi ẹnipe o tobi fun mi. 14 Ilu kekere kan wà, ati enia diẹ ninu rẹ̀; ọba nla kan si ṣigun tọ̀ ọ lọ, o si dótì i, o si mọ ile-iṣọ ti o tobi tì i. 15 A si ri ọkunrin talaka ọlọgbọ́n ninu rẹ̀, on si fi ọgbọ́n rẹ̀ gbà ilu na silẹ; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o ranti ọkunrin talaka na. 16 Nigbana ni mo wipe, Ọgbọ́n san jù agbara lọ; ṣugbọn a kẹgan ọgbọ́n ọkunrin talaka na, ohùn rẹ̀ kò si to òke. 17 A ngbọ́ ọ̀rọ ọlọgbọ́n enia ni pẹlẹ jù igbe ẹniti njẹ olori ninu awọn aṣiwère. 18 Ọgbọ́n san jù ohun-elo ogun: ṣugbọn ẹ̀lẹṣẹ kan o ba ohun didara pupọ jẹ.

Oniwasu 10

1 OKÚ eṣinṣin o mu ororo-ikunra alapolu bajẹ ki o ma run õrùn buburu: bẹ̃ni wère diẹ wuwo jù ọgbọ́n ati ọlá lọ. 2 Aiya ọlọgbọ́n mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ṣugbọn aiya aṣiwère li ọwọ òsi rẹ̀. 3 Ati pẹlu nigbati ẹniti o ṣiwère ba nrìn li ọ̀na, ọgbọ́n rẹ̀ a fò lọ, on a si wi fun olukuluku enia pe aṣiwère li on. 4 Bi ọkàn ijoye ba ru si ọ, máṣe fi ipò rẹ silẹ; nitoripe itũbá ama tù ẹ̀ṣẹ nla. 5 Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá. 6 A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin. 7 Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ. 8 Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán. 9 Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu. 10 Bi irin ba kújú, ti on kò si pọn oju rẹ̀, njẹ ki on ki o fi agbara si i; ṣugbọn ère ọgbọ́n ni lati fi ọ̀na hàn. 11 Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju. 12 Ọ̀rọ ẹnu ọlọgbọ̀n li ore-ọfẹ; ṣugbọn ète aṣiwère ni yio gbe ara rẹ̀ mì. 13 Ipilẹṣẹ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni wère: ati opin ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni isinwin iparun. 14 Aṣiwère pẹlu kún fun ọ̀rọ pupọ: enia kò le sọ ohun ti yio ṣẹ; ati ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀, tali o le wi fun u? 15 Lãla aṣiwère da olukuluku wọn li agara, nitoriti kò mọ̀ bi a ti lọ si ilu. 16 Egbé ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba ṣe ọmọde, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun ni kutukutu. 17 Ibukún ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba jẹ ọmọ ọlọlá, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun li akoko ti o yẹ, fun ilera ti kì si iṣe fun ọti amupara! 18 Nipa ilọra pupọ igi ile a hù; ati nipa ọlẹ ọwọ, ile a si ma jò. 19 Ẹrín li a nsàse fun, ati ọti-waini ni imu inu alãye dùn: owo si ni idahùn ohun gbogbo. 20 Máṣe bu ọba, ki o má ṣe ninu èro rẹ; máṣe bu ọlọrọ̀ ni iyẹwu rẹ; nitoripe ẹiyẹ oju-ọrun yio gbe ohùn na lọ, ohun ti o ni iyẹ-apá yio si sọ ọ̀ran na.

Oniwasu 11

1 FUN onjẹ rẹ si oju omi; nitoriti iwọ o ri i lẹhin ọjọ pupọ. 2 Fi ipin fun meje ati fun mẹjọ pẹlu, nitoriti iwọ kò mọ̀ ibi ti yio wà laiye. 3 Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe. 4 Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ kì yio funrugbin; ati ẹniti o si nwòju awọsanma kì yio ṣe ikore. 5 Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo. 6 Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna. 7 Nitõtọ imọlẹ dùn ati ohun didara ni fun oju lati wò õrùn. 8 Ṣugbọn bi enia wà li ọ̀pọlọpọ ọdun, ti o si nyọ̀ ninu gbogbo wọn, sibẹ, jẹ ki o ranti ọjọ òkunkun pe nwọn o pọ̀. Ohun gbogbo ti mbọ̀, asan ni. 9 Mã yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu ewe rẹ; ki o si jẹ ki ọkàn rẹ ki o mu ọ laraya li ọjọ ewe rẹ, ki o si ma rìn nipa ọ̀na ọkàn rẹ ati nipa irí oju rẹ; ṣugbọn iwọ mọ̀ eyi pe, nitori nkan wọnyi Ọlọrun yio mu ọ wá si idajọ. 10 Nitorina ṣi ibinujẹ kuro li aiya rẹ, ki o si mu ibi kuro li ara rẹ: nitoripe asan ni igba-ewe ati ọmọde.

Oniwasu 12

1 RANTI ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inudidùn ninu wọn; 2 Nigbati õrùn, tabi imọlẹ, tabi oṣupa tabi awọn irawọ kò ti iṣu òkunkun, ati ti awọsanma kò ti itun pada lẹhin òjo: 3 Li ọjọ ti awọn oluṣọ ile yio warìri, ati ti awọn ọkunrin alagbara yio tẹri wọn ba, awọn õlọ̀ yio si dakẹ nitoriti nwọn kò to nkan, ati awọn ti nwode loju ferese yio ṣu òkunkun, 4 Ti ilẹkun yio si se ni igboro, nigbati iró ọlọ yio rẹlẹ, ti yio si dide li ohùn kike ẹiyẹ, ati ti gbogbo awọn ọmọbinrin orin yio rẹ̀ silẹ; 5 Ati pẹlu ti nwọn o bẹ̀ru ibi ti o ga, ti iwariri yio si wà li ọ̀na, ati ti igi almondi yio tanna, ti ẹlẹnga yio di ẹrù, ti ifẹ yio si ṣá: nitoriti ọkunrin nlọ si ile rẹ̀ pipẹ, awọn aṣọ̀fọ yio si ma yide kakiri. 6 Tabi ki okùn fadaka ki o to tu, tabi ki ọpọn wura ki o to fọ, tabi ki ìṣa ki o to fọ nibi isun, tabi ki ayika-kẹkẹ ki o to kán nibi kanga. 7 Nigbana ni erupẹ yio pada si ilẹ bi o ti wà ri, ẹmi yio si pada tọ̀ Ọlọrun ti o fi i funni. 8 Asan ninu asan, oniwasu wipe, gbogbo rẹ̀ asan ni. 9 Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ. 10 Oniwasu wadi ati ri ọ̀rọ didùn eyiti a si kọ, ohun iduro-ṣinṣin ni, ani ọ̀rọ otitọ. 11 Ọ̀rọ ọlọgbọ́n dabi ẹgún, ati awọn olori akojọ-ọ̀rọ bi iṣó ti a kàn, ti a nfi fun ni lati ọwọ oluṣọ-agutan kan wá. 12 Ati siwaju, lati inu eyi, ọmọ mi, ki o gbà ìmọran: ninu kikọ iwe pupọ, opin kò si: ati iwe kikà pupọ li ãrẹ̀ ara. 13 Opin gbogbo ọ̀rọ na ti a gbọ́ ni pe: Bẹ̀ru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ̀ mọ́: nitori eyi ni fun gbogbo enia. 14 Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.

Orin 1

1 ORIN awọn orin ti iṣe ti Solomoni.

Orin Kinni

2 Jẹ ki o fi ifẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mi li ẹnu nitori ifẹ rẹ sàn jù ọti-waini lọ. 3 Nitoriti õrun ikunra rere rẹ, orukọ rẹ dabi ikunra ti a tú jade, nitorina ni awọn wundia ṣe fẹ ọ. 4 Fà mi, awa o sare tọ̀ ọ: ọba ti mu mi wá sinu iyẹwù rẹ̀: awa o yọ̀, inu wa o si dùn si ọ, awa o ranti ifẹ rẹ jù ọti-waini lọ: nwọn fẹ ọ nitõtọ. 5 Emi dú, ṣugbọn mo li ẹwà, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi awọn agọ Kedari, bi awọn aṣọ-tita Solomoni. 6 Máṣe wò mi, nitori pe mo dú, nitori pe õrùn ti bojuwò mi: awọn ọmọ iyá mi binu si mi; nwọn fi mi ṣe oluṣọ ọgba-ajara; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju. 7 Wi fun mi, Iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ, nibiti iwọ nṣọ agutan; nibiti iwọ nmu agbo-ẹran rẹ simi li ọsan; ki emi ki o má ba dabi alãrẹ̀ ti o ṣina kiri pẹlu agbo-ẹran awọn ẹgbẹ́ rẹ. 8 Bi iwọ kò ba mọ̀, Iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin, jade lọ ni ipasẹ agbo-ẹran, ki iwọ ki o si bọ́ awọn ọmọ ewurẹ rẹ lẹba agọ awọn aluṣọ-agutan. 9 Olufẹ mi, mo ti fi ọ we ẹṣin mi ninu kẹkẹ́ Farao. 10 Ẹrẹkẹ́ rẹ li ẹwà ninu ọwọ́ ohun ọṣọ́, ọrùn rẹ ninu ilẹkẹ. 11 Awa o ṣe ọwọ́ ohun ọṣọ́ wura fun ọ, pẹlu ami fadaka. 12 Nigbati ọba wà ni ibujoko ijẹun rẹ̀, ororo mi rán õrun rẹ̀ jade. 13 Idi ojia ni olufẹ ọ̀wọ́n mi si mi; on o ma gbe ãrin ọmu mi. 14 Olufẹ mi ri si mi bi ìdi ìtànná igi kipressi ni ọgba-ajara Engedi. 15 Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; wò o, iwọ li ẹwà: iwọ li oju àdaba. 16 Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi, nitõtọ, o wuni: ibusun wa pẹlu ni itura. 17 Igi kedari ni iti-igi ile wa, igi firi si ni ẹkẹ́ wa.

Orin 2

1 EMI ni itanná eweko Ṣaroni, ati itanná lili awọn afonifoji. 2 Bi itanná lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin. 3 Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu. 4 O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi. 5 Fi akara didùn da mi duro, fi eso igi tù mi ni inu: nitori aisàn ifẹ nṣe mi. 6 Ọwọ osì rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra. 7 Mo fi awọn abo egbin, ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.

Orin Keji

8 Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké. 9 Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà. 10 Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ. 11 Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ. 12 Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa. 13 Igi ọ̀pọtọ so eso titun, awọn àjara funni ni õrun daradara nipa itanná wọn. Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ. 14 Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà. 15 Mu awọn kọ̀lọkọlọ fun wa, awọn kọ̀lọkọlọ kékeké ti mba àjara jẹ: nitori àjara wa ni itanná. 16 Olufẹ mi ni temi, emi si ni tirẹ̀: o njẹ lãrin awọn lili. 17 Titi ìgba itura ọjọ, titi ojiji yio fi salọ, yipada, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin lori awọn oke Beteri.

Orin 3

1 LI oru lori akete mi, mo wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i. 2 Emi o dide nisisiyi, emi o si rìn lọ ni ilu, ni igboro, ati li ọ̀na gbòro ni emi o wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i. 3 Awọn oluṣọ ti nrìn ilu yika ri mi: mo bère pe, Ẹ ha ri ẹniti ọkàn mi fẹ bi? 4 Ṣugbọn bi mo ti fi wọn silẹ gẹrẹ ni mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: mo dì i mu, emi kò si jọ̃rẹ̀ lọwọ, titi mo fi mu u wá sinu ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o loyun mi. 5 Mo fi awọn abo egbin ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ji i, titi yio fi wù u.

Orin Kẹta

6 Tani eyi ti nti ijù jade wá bi ọwọ̀n ẽfin, ti a ti fi ojia ati turari kùn lara, pẹlu gbogbo ipara olõrun oniṣowo? 7 Wo akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akọni enia li o yi i ka ninu awọn akọni Israeli. 8 Gbogbo wọn li o di idà mu, nwọn gbọ́n ọgbọ́n ogun: olukulùku kọ́ idà rẹ̀ nitori ẹ̀ru li oru. 9 Solomoni, ọba, ṣe akete nla fun ara rẹ̀ lati inu igi Lebanoni. 10 O fi fadaka ṣe ọwọ̀n rẹ̀, o fi wura ṣe ibi ẹhin rẹ̀, o fi elese aluko ṣe ibujoko rẹ̀, inu rẹ̀ li o fi ifẹ tẹ́ nitori awọn ọmọbinrin Jerusalemu. 11 Ẹ jade lọ, Ẹnyin ọmọbinrin Sioni, ki ẹ si wò Solomoni, ọba, ti on ti ade ti iya rẹ̀ fi de e li ọjọ igbeyawo rẹ̀, ati li ọjọ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Orin 4

1 WÒ o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi: wò o, iwọ li ẹwà; iwọ li oju àdaba labẹ iboju rẹ: irun rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ, ti o dubulẹ lori òke Gileadi. 2 Ehin rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ ti a rẹ́ ni irun, ti o gòke lati ibi iwẹ̀ wá, olukulùku wọn bi èjirẹ, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn. 3 Ete rẹ dabi owu òdodo, ohùn rẹ si dùn: ẹ̀rẹkẹ rẹ si dabi ẹlà pomegranate kan labẹ iboju rẹ. 4 Ọrùn rẹ dabi ile-iṣọ Dafidi ti a kọ́ fun ihamọra, lori eyi ti a fi ẹgbẹrun apata kọ́, gbogbo wọn jẹ asà awọn alagbara. 5 Ọmu rẹ mejeji dabi abo egbin kekere meji ti iṣe èjirẹ, ti njẹ lãrin itanna lili. 6 Titi ọjọ yio fi rọ̀, ti ojiji yio si fi fò lọ, emi o lọ si òke nla ojia, ati si òke kékeké turari. 7 Iwọ li ẹwà gbogbo, olufẹ mi; kò si abawọ́n lara rẹ! 8 Ki a lọ kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lọ kuro ni Lebanoni: wò lati ori òke Amana, lati ori òke Ṣeniri ati Hermoni, lati ibi ihò kiniun, lati òke awọn ẹkùn. 9 Iwọ ti gbà mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo! iwọ ti fi ọkan ninu ìwo oju rẹ, ati ọkan ninu ẹwọ̀n ọrùn rẹ gbà mi li ọkàn. 10 Ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo! ifẹ rẹ ti sàn jù ọti-waini to! õrùn ikunra rẹ si jù turari gbogbo lọ. 11 Iyawo! ète rẹ nkán bi afara-oyin: oyin ati wàra mbẹ labẹ ahọn rẹ; õrun aṣọ rẹ si dabi õrun Lebanoni. 12 Ọgbà ti a sọ ni arabinrin mi, iyawo! isun ti a sé, orisun ti a fi edidi dí. 13 Ohun gbigbìn rẹ agbala pomegranate ni, ti on ti eso ti o wunni; kipressi ati nardi. 14 Nardi ati saffroni; kalamusi, kinnamoni, pẹlu gbogbo igi turari; ojia ati aloe, pẹlu gbogbo awọn olori olõrun didùn. 15 Orisun ninu ọgba kanga omi iyè, ti nṣan lati Lebanoni wá. 16 Ji afẹfẹ ariwa; si wá, iwọ ti gusu; fẹ́ sori ọgbà mi, ki õrun inu rẹ̀ le fẹ́ jade. Jẹ ki olufẹ mi wá sinu ọgbà rẹ̀, ki o si jẹ eso didara rẹ̀.

Orin 5

1 MO de inu ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo! mo ti kó ojia mi pẹlu õrùn didùn mi jọ; mo ti jẹ afara mi pẹlu oyin mi; mo ti mu ọti-waini mi pẹlu wàra mi: Ẹ jẹun, ẹnyin ọrẹ́; mu, ani mu amuyo, ẹnyin olufẹ.

Orin Kẹrin

2 Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru. 3 Mo ti bọ́ awọtẹlẹ mi; emi o ti ṣe gbe e wọ̀? mo ti wẹ̀ ẹsẹ̀ mi; emi o ti ṣe sọ wọn di aimọ́? 4 Olufẹ mi nawọ rẹ̀ lati inu ihò ilẹkùn, inu mi sì yọ si i. 5 Emi dide lati ṣilẹkun fun olufẹ mi, ojia si nkán lọwọ mi, ati ojia olõrùn didùn ni ika mi sori idimu iṣikà. 6 Mo ṣilẹkun fun olufẹ mi; ṣugbọn olufẹ mi ti fà sẹhin, o si ti lọ: aiya pá mi nigbati o sọ̀rọ, mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i, mo pè e, ṣugbọn on kò da mi lohùn. 7 Awọn oluṣọ ti nrìn ilu kiri ri mi, nwọn lù mi, nwọn sì ṣa mi lọgbẹ, awọn oluṣọ gbà iborùn mi lọwọ mi. 8 Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi ẹnyin ba ri olufẹ mi, ki ẹ wi fun u pe, aisan ifẹ nṣe mi. 9 Kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran ti iwọ fi nfi wa bú bẹ̃? 10 Olufẹ mi funfun, o si pọn, on ni ọlá jù ọ̀pọlọpọ lọ. 11 Ori rẹ̀ dabi wura ti o dara julọ, ìdi irun rẹ̀ dabi imọ̀ ọpẹ, o si du bi ẹiyẹ iwò. 12 Oju rẹ̀ dabi àdaba li ẹba odò, ti a fi wàra wẹ̀, ti o si ngbe inu alafia. 13 Ẹrẹ̀kẹ rẹ̀ dabi ebè turari, bi olõrùn didùn, ète rẹ̀ bi itanna lili, o nkán ojia olõrùn didùn. 14 Ọwọ rẹ̀ dabi oruka wura ti o tò ni berili yika, ara rẹ̀ bi ehin-erin didán ti a fi saffire bò. 15 Itan rẹ̀ bi ọwọ̀n marbili, ti a gbe ka ihò ìtẹbọ wura daradara; ìwo rẹ̀ dabi Lebanoni, titayọ rẹ̀ bi igi kedari. 16 Ẹnu rẹ̀ dùn rekọja: ani o wunni patapata. Eyi li olufẹ mi, eyi si li ọrẹ mi, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu.

Orin 6

1 NIBO ni olufẹ rẹ lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? nibo li olufẹ rẹ yà si? ki a le ba ọ wá a. 2 Olufẹ mi sọkalẹ lọ sinu ọgba rẹ̀, si ebè turari, lati ma jẹ̀ ninu ọgbà, ati lati ká itanna lili. 3 Emi ni ti olufẹ mi, olufẹ mi si ni ti emi: o njẹ̀ lãrin itanna lili.

Orin Karun-un

4 Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalemu, ṣugbọn o li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun. 5 Mu oju rẹ kuro lara mi nitori nwọn bori mi: irun rẹ si dabi ọwọ́ ewurẹ ti o dubulẹ ni Gileadi. 6 Ehin rẹ dabi ọwọ́ agutan ti ngòke lati ibi iwẹ̀ wá, ti olukuluku wọn bi ìbejì, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn. 7 Bi ẹ̀la eso-pomegranate kan ni ẹrẹkẹ rẹ ri lãrin iboju rẹ. 8 Ọgọta ayaba ni mbẹ, ati ọgọrin àle, ati awọn wundia lainiye. 9 Ọkan ni adaba mi, alailabawọn mi; on nikanṣoṣo ni ti iya rẹ̀, on ni ãyo ẹniti o bi i. Awọn ọmọbinrin ri i, nwọn si sure fun u; ani awọn ayaba ati awọn àle, nwọn si yìn i. 10 Tali ẹniti ntàn jàde bi owurọ, ti o li ẹwà bi oṣupa, ti o mọ́ bi õrun, ti o si li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun? 11 Emi sọkalẹ lọ sinu ọgba eso igi, lati ri awọn ẹka igi tutu afonifoji, ati lati ri bi ajara ba ruwe, ati bi igi-granate ba rudi. 12 Ki emi to mọ̀, ọkàn mi gbe mi ka ori kẹkẹ́ Amminadibu. 13 Pada, pada, Ṣulamite; pada, pada, ki awa ki o le wò ọ. Ẽṣe ti ẹnyin fẹ wò Ṣulamite bi ẹnipe orin ijó Mahanaimu.

Orin 7

1 Ẹsẹ rẹ ti li ẹwà to ninu bata, iwọ ọmọ-alade! orike itan rẹ dabi ohun ọṣọ́, iṣẹ ọwọ ọlọgbọ́n oniṣọna. 2 Iwọ́ rẹ dabi ago ti kò ṣe alaini ọti, ara rẹ dabi okiti alikama ti a fi lili yika. 3 Ọmú rẹ mejeji dabi abo ọmọ agbọnrin meji ti iṣe ìbejì. 4 Ọrùn rẹ dabi ile iṣọ ehin-erin; oju rẹ dabi adagun ni Heṣboni, lẹba ẹnu-bode Batrabbimu: imú rẹ dabi ile-iṣọ Lebanoni ti o kọju si ihà Damasku. 5 Ori rẹ dabi Karmeli lara rẹ, ati irun ori rẹ bi purpili; a fi aidì irun rẹ di ọba mu. 6 O ti li ẹwà to, o si ti dara to, iwọ olufẹ mi ninu adùn ifẹ! 7 Iduro rẹ yi dabi igi ọ̀pẹ ati ọmú rẹ bi ṣiri eso àjara. 8 Mo ni, emi o gùn ọ̀pẹ lọ, emi o di ẹka rẹ̀ mu: pẹlupẹlu nisisiyi ọmú rẹ pẹlu yio dabi ṣiri àjara, ati õrùn imú rẹ bi eso appili; 9 Ati ẹnu rẹ bi ọti-waini ti o dara jù, ti o sọkalẹ kẹlẹkẹlẹ fun olufẹ mi, ti o nmu ki etè awọn ti o sùn ki o sọ̀rọ. 10 Ti olufẹ mi li emi iṣe, ifẹ rẹ̀ si mbẹ si mi. 11 Wá, olufẹ mi, jẹ ki a lọ si pápa; jẹ ki a wọ̀ si iletò wọnni. 12 Jẹ ki a dide lọ sinu ọgba-àjara ni kutukutu; jẹ ki a wò bi àjara ruwe, bi itanná àjara ba là, ati bi igi granate ba rudi: nibẹ li emi o fi ifẹ mi fun ọ. 13 Awọn eso mandraki fun ni li õrùn, li ẹnu-ọ̀na wa ni onirũru eso ti o wunni, ọtun ati ogbologbo, ti mo ti fi pamọ́ fun ọ, iwọ olufẹ mi.

Orin 8

1 IWỌ iba jẹ dabi arakunrin fun mi, ti o mu ọmú iya mi! emi iba ri ọ lode emi iba fi ẹnu kò ọ lẹnu; lõtọ, nwọn kì ba fi mi ṣe ẹlẹya. 2 Emi iba fọnahàn ọ, emi iba mu ọ wá sinu ile iya mi, iwọ iba kọ́ mi: emi iba mu ọ mu ọti-waini õrùn didùn, ati oje eso granate mi. 3 Ọwọ osì rẹ̀ iba wà labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ iba si gbá mi mọra. 4 Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u. 5 Tani eyi ti ngòke lati aginju wá, ti o fi ara tì olufẹ rẹ̀? mo ji ọ dide labẹ igi eleso: nibẹ ni iya rẹ gbe bi ọ si, nibẹ li ẹniti o bi ọ gbe bi ọ si. 6 Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa. 7 Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata. 8 Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ? 9 Bi on ba ṣe ogiri, awa o kọ́ ile-odi fadaka le e lori: bi on ba si ṣe ẹnu-ọ̀na, awa o fi apako kedari dí i. 10 Ogiri ni mi, ọmú mi sì dabi ile-iṣọ: nigbana loju rẹ̀ mo dabi ẹniti o ri alafia. 11 Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀. 12 Ọgba-àjara mi, ti iṣe temi, o wà niwaju mi: iwọ Solomoni yio ni ẹgbẹrun fadaka, ati awọn ti nṣọ eso na yio ni igba. 13 Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu. 14 Yara, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin tabi ọmọ agbọnrin lori òke õrùn didùn.

Isaiah 1

1 IRAN Isaiah ọmọ Amosi, ti o rí nipa Juda ati Jerusalemu li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda.

OLUWA Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Wí

2 Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi. 3 Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu. 4 A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn. 5 Ẽṣe ti a o fi lù nyin si i mọ? ẹnyin o ma ṣọ̀tẹ siwaju ati siwaju: gbogbo ori li o ṣaisàn, gbogbo ọkàn li o si dakú. 6 Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn. 7 Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ. 8 Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti. 9 Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra. 10 Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin olori Sodomu; fi eti si ofin Ọlọrun wa, ẹnyin enia Gomorra. 11 Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ. 12 Nigbati ẹnyin wá lati fi ara hàn niwaju mi, tali o bere eyi lọwọ nyin, lati tẹ̀ agbalá mi? 13 Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ́: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà; ẹ̀ṣẹ ni, ani apèjọ ọ̀wọ nì. 14 Oṣù titun nyin ati ajọ ìdasilẹ nyin, ọkàn mi korira; nwọn jasi iyọlẹnu fun mi; o sú mi lati gbà wọn. 15 Nigbati ẹnyin si nà ọwọ́ nyin jade, emi o pa oju mi mọ fun nyin: nitõtọ, nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi kì yio gbọ́: ọwọ́ nyin kún fun ẹ̀jẹ. 16 Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu; 17 Kọ́ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbà ẹjọ opó rò. 18 Oluwa wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ̀: bi ẹ̀ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọ́n bi àlãri, nwọn o dabi irun-agutan. 19 Bi ẹnyin ba fẹ́ ti ẹ si gbọran, ẹnyin o jẹ ire ilẹ na: 20 Ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀, ti ẹ si ṣọ̀tẹ, a o fi idà run nyin: nitori ẹnu Oluwa li o ti wi i.

Ìlú tí Ó kún fún Ẹ̀ṣẹ̀

21 Ilu otitọ ha ti ṣe di àgbere! o ti kún fun idajọ ri; ododo ti gbe inu rẹ̀ ri; ṣugbọn nisisiyi, awọn apania. 22 Fadaka rẹ ti di ìdarọ́, ọti-waini rẹ ti dà lu omi: 23 Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn. 24 Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi. 25 Emi o yi ọwọ́ mi si ara rẹ, emi o si yọ́ ìdarọ́ rẹ kuro patapata, emi o si mu gbogbo tanganran rẹ kuro: 26 Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣãju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbẹ̀rẹ: lẹhin na, a o pè ọ ni, Ilu ododo, ilu otitọ. 27 Idajọ li a o fi rà Sioni pada, ati awọn ti o pada bọ̀ nipa ododo. 28 Iparun awọn alarekọja pẹlu awọn ẹlẹṣẹ yio wà pọ̀, ati awọn ti o kọ̀ Oluwa silẹ li a o parun. 29 Nitoriti oju yio tì wọn niti igi-nla ti ẹnyin ti fẹ, a o si dãmu nyin niti ọgbà ti ẹnyin ti yàn. 30 Nitori ẹnyin o dabi igi-nla ti ewe rẹ̀ rọ, ati bi ọgbà ti kò ni omi. 31 Alagbara yio si dabi ògùṣọ̀, iṣẹ rẹ̀ yio si dabi ẹta-iná, ati awọn mejeji yio jọ jona pọ̀, ẹnikẹni kì yio si pa wọn.

Isaiah 2

Alaafia Ayérayé

1 Ọ̀RỌ ti Isaiah ọmọ Amosi ri nipa Juda ati Jerusalemu. 2 Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhìn, a o fi òke ile Oluwa kalẹ lori awọn òke nla, a o si gbe e ga ju awọn òke kékèké lọ; gbogbo orilẹ-ède ni yio si wọ́ si inu rẹ̀. 3 Ọ̀pọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; On o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa rẹ̀; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. 4 On o si dajọ lãrin awọn orilẹ-ède, yio si ba ọ̀pọlọpọ enia wi: nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o si fi ọ̀kọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. 5 Ara ile Jakobu, ẹ wá, ẹ jẹ́ ka rìn ninu imọlẹ Ọluwa.

A óo pa Ìgbéraga Run

6 Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò. 7 Ilẹ wọn pẹlu kún fun fadakà ati wurà; bẹ̃ni kò si opin fun iṣura wọn; ilẹ wọn si kun fun ẹṣin, bẹ̃ni kò si opin fun kẹkẹ́ ogun wọn. 8 Ilẹ wọn kún fun oriṣa pẹlu; nwọn mbọ iṣẹ ọwọ́ ara wọn, eyiti ika awọn tikalawọn ti ṣe. 9 Enia lasan si foribalẹ, ẹni-nla si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; nitorina má ṣe darijì wọn. 10 Wọ̀ inu apata lọ, ki o si fi ara rẹ pamọ ninu ekuru, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀. 11 A o rẹ̀ ìwo giga enia silẹ, a o si tẹ̀ ori igberaga enia ba, Oluwa nikanṣoṣo li a o gbe ga li ọjọ na. 12 Nitori ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun yio wà lori olukuluku ẹniti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹniti a gbe soke, on li a o si rẹ̀ silẹ. 13 Lori gbogbo igi kedari Lebanoni, ti o ga, ti a sì gbe soke, ati lori gbogbo igi-nla Baṣani. 14 Ati lori gbogbo òke giga, ati lori gbogbo òke kékèké ti a gbe soke. 15 Ati lori gbogbo ile-iṣọ giga ati lori gbogbo odi, 16 Ati lori gbogbo ọkọ̀ Tarṣiṣi, ati lori gbogbo awòran ti o wuni, 17 A o si tẹ̀ ori igberaga enia balẹ, irera awọn enia li a o si rẹ̀ silẹ; Oluwa nikanṣoṣo li a o gbega li ọjọ na. 18 Awọn òriṣa ni yio si parun patapata. 19 Nwọn o si wọ̀ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ìbẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀, nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji. 20 Li ọjọ na, enia yio jù òriṣa fadakà rẹ̀, ati òriṣa wurà rẹ̀, ti nwọn ṣe olukuluku wọn lati ma bọ, si ekute ati si àdan, 21 Lati lọ sinu pàlapala apata, ati soke apata sisán, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀; nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji. 22 Ẹ simi lẹhìn enia, ẹmi ẹniti o wà ni ihò imu rẹ̀; nitori ninu kini a le kà a si?

Isaiah 3

Ìdàrúdàpọ̀ Ní Jerusalẹmu

1 KIYESI i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, mu idaduro ati ọpá kuro ninu Jerusalemu ati Juda, gbogbo idaduro onjẹ, ati gbogbo idaduro omi. 2 Alagbara ọkunrin, ati jagunjagun, onidajọ, ati wolĩ, ati amoye, ati agbà. 3 Balogun ãdọta, ati ọkunrin ọlọla, ati igbìmọ, ati oniṣọ̀na, ati alasọdùn. 4 Awọn ọmọde li emi o fi ṣe ọmọ-alade wọn, awọn ọmọ-ọwọ ni yio si ma ṣe akoso wọn. 5 A o si ni awọn enia lara, olukuluku lọwọ ẹnikeji, ati olukuluku lọwọ aladugbo rẹ̀; ọmọde yio huwà igberaga si àgba, ati alailọla si ọlọla. 6 Nigbati enia kan yio di arakunrin rẹ̀ ti ile baba rẹ̀ mu, wipe, Iwọ ni aṣọ, mã ṣe alakoso wa, ki o si jẹ ki iparun yi wà labẹ ọwọ́ rẹ. 7 Lọjọ na ni yio bura, wipe, Emi kì yio ṣe alatunṣe; nitori ni ile mi kò si onjẹ tabi aṣọ: máṣe fi emi ṣe alakoso awọn enia. 8 Nitori Jerusalemu di iparun, Juda si ṣubu: nitori ahọn wọn ati iṣe wọn lòdi si Oluwa, lati mu oju ogo rẹ̀ binu. 9 Iwò oju wọn njẹri si wọn; nwọn si nfi ẹ̀ṣẹ wọn hàn bi Sodomu, nwọn kò pa a mọ. Egbe ni fun ọkàn wọn! nitori nwọn ti fi ibi san a fun ara wọn. 10 Ẹ sọ fun olododo pe, yio dara fun u: nitori nwọn o jẹ eso iṣe wọn. 11 Egbe ni fun enia buburu! yio buru fun u: nitori ere ọwọ́ rẹ̀ li a o fi fun u. 12 Niti awọn enia mi awọn ọmọde ni aninilara wọn, awọn obinrin si njọba wọn. A! enia mi, awọn ti nyẹ ọ si mu ọ ṣìna, nwọn si npa ipa-ọ̀na rẹ run.

OLUWA Dá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Lẹ́jọ́

13 Oluwa dide duro lati wijọ, o si dide lati da awọn enia li ẹjọ. 14 Oluwa yio ba awọn agbà enia rẹ̀ lọ sinu idajọ, ati awọn ọmọ-alade inu wọn: nitori ẹnyin ti jẹ ọ̀gba àjara nì run: ẹrù awọn talakà mbẹ ninu ile nyin. 15 Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Kili ẹnyin rò ti ẹ fi fọ́ awọn enia mi tutu, ti ẹ si fi oju awọn talakà rinlẹ?

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Obinrin Jerusalẹmu

16 Pẹlupẹlu Oluwa wipe, Nitori awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, ti nwọn si nrìn pẹlu ọrùn giga ati oju ifẹkufẹ, ti nwọn nrìn ti nwọn si nyan bi nwọn ti nlọ, ti nwọn si njẹ ki ẹsẹ wọn ró woro: 17 Nitorina Oluwa yio fi ẽpá lu atàri awọn ọmọbinrin Sioni, Oluwa yio si fi ihoho wọn hàn. 18 Li ọjọ na Oluwa yio mu ogo ṣaworo wọn kuro, ati awọn ọṣọ́ wọn, ati iweri wọn bi oṣupa. 19 Ati ẹ̀wọn, ati jufù, ati ìboju, 20 Ati akẹtẹ̀, ati ohun ọṣọ́-ẹsẹ, ati ọjá-ori, ati ago olõrùn didùn, ati oruka eti, 21 Oruka, ati ọṣọ́-imu, 22 Ipãrọ̀ aṣọ wiwọ, ati aṣọ ilekè, ati ibọ̀run, ati àpo, 23 Awòjiji, ati aṣọ ọ̀gbọ daradara, ati ibòri ati ibòju, 24 Yio si ṣe pe, õrun buburu yio wà dipò õrun didùn; akisà ni yio si dipò amùre; ori pipá ni yio si dipò irun didì daradara; sisan aṣọ ọ̀fọ dipò igbaiya, ijoná yio si dipò ẹwà. 25 Awọn ọkunrin rẹ yio ti ipa idà ṣubu, ati awọn alagbara rẹ loju ogun. 26 Awọn bodè rẹ̀ yio pohùnrere ẹkun, nwọn o si ṣọ̀fọ; ati on, nitori o di ahoro, yio joko ni ilẹ.

Isaiah 4

1 ATI li ọjọ na obinrin meje yio dimọ́ ọkunrin kan, wipe, Awa o jẹ onjẹ ara wa, awa o si wọ̀ aṣọ ara wa: kìkì pe, jẹ ki a fi orukọ rẹ pè wa, lati mu ẹgàn wa kuro.

A óo Tún Jerusalẹmu Kọ́

2 Li ọjọ na ni ẹka Oluwa yio ni ẹwà on ogo, eso ilẹ yio si ni ọla, yio si dara fun awọn ti o sálà ni Israeli. 3 Yio si ṣe, pe, ẹniti a fi silẹ ni Sioni, ati ẹniti o kù ni Jerusalemu, li a o pè ni mimọ́, ani orukọ olukuluku ẹniti a kọ pẹlu awọn alãye ni Jerusalemu. 4 Nigbati Oluwa ba ti wẹ̀ ẹgbin awọn ọmọbinrin Sioni nù, ti o si ti fọ ẹ̀jẹ Jerusalemu kuro li ãrin rẹ̀ nipa ẹmi idajọ, ati nipa ẹmi ijoná. 5 Lori olukuluku ibùgbe oke Sioni, ati lori awọn apejọ rẹ̀, li Oluwa yio si da awọsanma, ati ẹ̃fin li ọsan, ati didan ọwọ́ iná li oru: nitori àbò yio wá lori gbogbo ogo. 6 Agọ kan yio si wà fun ojiji li ọsan kuro ninu oru, ati fun ibi isasi, ati fun ãbo kuro ninu ijì, ati kuro ninu ojò.

Isaiah 5

Orin Ọgbà Àjàrà

1 NISISIYI, emi o kọ orin si olufẹ ọwọ́n mi, orin olùfẹ mi ọwọ́n niti ọ̀gba àjara rẹ̀. Olufẹ ọwọ́n mi ni ọ̀gba àjara lori okè ẹlẹtù loju: 2 O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so. 3 Njẹ nisisiyi, ẹnyin ara Jerusalemu ati ẹnyin ọkunrin Juda, emi bẹ̀ nyin, ṣe idajọ lãrin mi, ati lãrin ọ̀gba àjara mi. 4 Kini a ba ṣe si ọ̀gba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rẹ̀, nigbati mo wò pe iba so eso, ẽṣe ti o fi so eso kikan? 5 Njẹ nisisiyi, ẹ wá na, emi o sọ ohun ti emi o ṣe si ọ̀gba àjara mi fun nyin: emi o mu ọ̀gba rẹ̀ kuro, a o si jẹ ẹ run, emi o wo ogiri rẹ̀ lu ilẹ, a o si tẹ̀ ẹ mọlẹ. 6 Emi o si sọ ọ di ahoro, a kì yio tọ́ ẹka rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio wà a, ṣugbọn ẹ̀wọn ati ẹ̀gún ni yio ma hù nibẹ, emi o si paṣẹ fun awọsanma ki o má rọjò sori rẹ̀. 7 Nitori ọ̀gba àjara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ile Israeli, ati awọn ọkunrin Juda ni igi-gbìgbin ti o wù u, o reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.

Ìwà Burúkú Eniyan

8 Egbe ni fun awọn ti o ni ile kún ile, ti nfi oko kún oko, titi ãyè kò fi si mọ, ki nwọn bà le nikan wà li ãrin ilẹ aiye! 9 Li eti mi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ pe, Nitõtọ ọ̀pọ ile ni yio di ahoro, ile nla ati daradara laisi olugbe. 10 Nitõtọ ìwọn akeri mẹwa ọ̀gba àjara yio mu òṣuwọn bati kan wá, ati òṣuwọn irugbìn homeri kan yio mu òṣuwọn efa kan wá. 11 Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona! 12 Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀. 13 Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ. 14 Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀. 15 Enia lasan li a o rẹ̀ silẹ, ati ẹni-alagbara li a o rẹ̀ silẹ, oju agberaga li a o si rẹ̀ silẹ. 16 Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun li a o gbe ga ni idajọ, ati Ọlọrun Ẹni-Mimọ́ yio jẹ mimọ́ ninu ododo. 17 Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ. 18 Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ. 19 Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ. 20 Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò! 21 Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn! 22 Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile: 23 Awọn ẹniti o da are fun ẹni-buburu nitori ère, ti nwọn si mu ododo olododo kuro li ọwọ́ rẹ̀. 24 Nitorina bi iná ti ijo akekù koriko run, ti ọwọ́ iná si ijo iyàngbo; bẹ̃ni egbò wọn yio da bi rirà; itanna wọn yio si gòke bi ekuru; nitori nwọn ti ṣá ofin Oluwa awọn ọmọ-ogun tì, nwọn si ti gàn ọ̀rọ Ẹni-Mimọ Israeli. 25 Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ. 26 Yio si gbe ọpágun soke si awọn orilẹ-ède ti o jìna, yio si kọ si wọn lati opin ilẹ wá, si kiyesi i, nwọn o yara wá kánkán. 27 Kò si ẹniti yio rẹ̀, tabi ti yio kọsẹ ninu wọn, kò si ẹniti yio tõgbe tabi ti yio sùn: bẹ̃ni amùre ẹgbẹ wọn kì yio tu, bẹ̃ni okùn bàta wọn kì yio ja. 28 Awọn ẹniti ọfà wọn mu, ti gbogbo ọrun wọn si kàn, a o ka patakò ẹsẹ ẹṣin wọn si okuta akọ, ati kẹkẹ́ wọn bi ãja. 29 Kike wọn yio dabi ti kiniun, nwọn o ma ke bi awọn ọmọ kiniun, nitõtọ nwọn o ma ke, nwọn o si di ohun ọdẹ na mu, nwọn a si gbe e lọ li ailewu, kò si ẹnikan ti yio gbà a. 30 Ati li ọjọ na nwọn o ho si wọn, bi hiho okun: bi ẹnikan ba si wo ilẹ na, kiyesi i, okùnkun ati ipọnju, imọlẹ si di okùnkun ninu awọsanma dudu rẹ̀.

Isaiah 6

Ọlọrun Pe Aisaya láti jẹ́ Wolii

1 LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili. 2 Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọ̃kan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bò oju rẹ̀, o si fi meji bò ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò. 3 Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀. 4 Awọn òpo ilẹ̀kun si mì nipa ohùn ẹniti o ke, ile na si kún fun ẹ̃fin. 5 Nigbana ni mo wipe, Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jẹ́ ẹni alaimọ́ etè, mo si wà lãrin awọn enia alaimọ́ etè, nitoriti oju mi ti ri Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun. 6 Nigbana ni ọkan ninu awọn serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹṣẹ́-iná li ọwọ́ rẹ̀, ti o ti fi ẹmú mu lati ori pẹpẹ wá. 7 O si fi kàn mi li ẹnu, o si wipe, Kiyesi i, eyi ti kàn etè rẹ, a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọ ẹ̀ṣẹ rẹ nù. 8 Emi si gbọ́ ohùn Oluwa pẹlu wipe, Tali emi o rán, ati tani yio si lọ fun wa? Nigbana li emi wipe, Emi nĩ; rán mi. 9 On si wipe, Lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, Ni gbigbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri, ẹ ri, ṣugbọn ẹnyin ki yio si mọ̀ oye. 10 Mu ki aiya awọn enia yi ki o sebọ́, mú ki eti wọn ki o wuwo, ki o si di wọn li oju, ki nwọn ki o má ba fi eti wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba mu wọn li ara dá. 11 Nigbana ni emi wipe, Oluwa, yio ti pẹ to? O si dahùn pe, Titi awọn ilu-nla yio fi di ahoro, li aisi olugbe, ati awọn ile li aisi enia, ati ilẹ yio di ahoro patapata. 12 Titi Oluwa yio fi ṣi awọn enia na kuro lọ rére, ti ikọ̀silẹ nla yio si wà ni inu ilẹ na. 13 Ṣugbọn sibẹ, idamẹwa yio wà ninu rẹ̀, yio si padà, yio si di rirun, bi igi teili, ati bi igi oakù eyiti ọpá wà ninu wọn, nigbati ewe wọn ba rẹ̀: bẹ̃ni iru mimọ́ na yio jẹ ọpá ninu rẹ̀.

Isaiah 7

Isaiah Jíṣẹ́ OLUWA fún Ahasi Ọba

1 O si ṣe li ọjọ Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah, ọba Juda, ti Resini, ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah, ọba Israeli, gokè lọ si Jerusalemu lati jà a li ogun, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀. 2 A si sọ fun ile Dafidi pe, Siria ba Efraimu dìmọlú. Ọkàn rẹ̀ si mì, ati ọkàn awọn enia rẹ̀ bi igi igbo ti imì nipa ẹfũfu. 3 Oluwa si sọ fun Isaiah pe, Jade nisisiyi, lọ ipade Ahasi, iwọ, ati Ṣeaja-ṣubu ọmọ rẹ, ni ipẹkun oju iṣàn ikũdu ti apa oke, li opopo pápa afọṣọ; 4 Si sọ fun u pe, Kiyesara, ki o si gbe jẹ, má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe jaiya nitori ìru meji igi iná ti nrú ẹ̃fin wọnyi nitori ibinu mimuna Resini pẹlu Siria, ati ti ọmọ Remaliah. 5 Nitori Siria, Efraimu, ati ọmọ Remaliah ti gbìmọ ibi si ọ wipe. 6 Ẹ jẹ ki a gòke lọ si Juda, ki a si bà a ninu jẹ, ẹ si jẹ ki a ṣe ihò ninu rẹ̀ fun ara wa, ki a si gbe ọba kan kalẹ lãrin rẹ̀, ani ọmọ Tabeali: 7 Bayi ni Oluwa Jehofah wi, Ìmọ na kì yio duro, bẹ̃ni ki yio ṣẹ. 8 Nitori ori Siria ni Damasku, ori Damasku si ni Resini; ninu ọdun marunlelọgọta li a o fọ Efraimu ti ki yio si jẹ́ enia mọ. 9 Ori Efraimu si ni Samaria, ori Samaria si ni ọmọ Remaliah. Bi ẹnyin ki yio ba gbagbọ́, lotitọ, a ki yio fi idi nyin mulẹ.

Àmì Imanuẹli

10 Oluwa si tun sọ fun Ahasi pe, 11 Bere àmi kan lọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ; bere rẹ̀, ibã jẹ ni ọgbun tabi li okè. 12 Ṣugbọn Ahasi wipe, Emi ki yio bere, bẹ̃ni emi ki yio dán Oluwa wò. 13 On si wipe, Ẹ gbọ́ nisisiyi ẹnyin ara ile Dafidi, iṣe ohun kekere fun nyin lati dá enia lagara, ṣugbọn ẹnyin o ha si dá Ọlọrun mi lagara pẹlu bi? 14 Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli. 15 Ori-amọ ati oyin ni yio ma jẹ, ki o le ba mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire. 16 Nitoripe, ki ọmọ na ki o to mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire, ilẹ ti iwọ korira yio di ikọ̀silẹ lọdọ ọba rẹ̀ mejeji. 17 Oluwa yio si mu ọjọ ti kò si bẹ̃ ri wá sori rẹ ati sori awọn enia rẹ, ati sori ile baba rẹ, lati ọjọ ti Efraimu ti lọ kuro lọdọ Juda, ani ọba Assiria. 18 Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio kọ si eṣinṣin ti o wà li apa ipẹkun odo ṣiṣàn nlanla Egipti, ati si oyin ti o wà ni ilẹ Assiria. 19 Nwọn o si wá, gbogbo wọn o si bà sinu afonifojì ijù, ati sinu pàlapala okuta, ati lori gbogbo ẹgun, ati lori eweko gbogbo. 20 Li ọjọ kanna ni Oluwa yio fi abẹ ti a yá, eyini ni, awọn ti ihà keji odo nì, ọba Assiria, fá ori ati irun ẹsẹ, yio si run irungbọn pẹlu. 21 Yio si ṣe li ọjọ na, enia kan yio si tọ́ ọmọ malu kan ati agutan meji; 22 Yio si ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ wàra ti nwọn o mu wá, yio ma jẹ ori-amọ; nitori ori-amọ ati oyin ni olukulùku ti o ba kù ni ãrin ilẹ na yio ma jẹ. 23 Yio si ṣe li ọjọ na, ibi gbogbo yio ri bayi pe, ibi ti ẹgbẹrun àjara ti wà fun ẹgbẹrun owo fadakà yio di ti ẹwọn ati ẹgun. 24 Pẹlu ọfà ati ọrun ni enia yio wá ibẹ, nitoripe gbogbo ilẹ na yio di ẹwọn ati ẹgun. 25 Ati lori gbogbo okè kékèké ti a o fi ọkọ́ tu, ẹ̀ru ẹ̀wọn ati ẹ̀gun ki yio de ibẹ̀: ṣugbọn yio jẹ ilu ti a ndà malũ lọ, ati ibi itẹ̀mọlẹ fun awọn ẹran kékèké.

Isaiah 8

Ọmọ Aisaya jẹ́ Àmì fún Àwọn Eniyan

1 PẸLUPẸLU Oluwa wi fun mi pe, Iwọ mu iwe nla kan, ki o si fi kalamu enia kọwe si inu rẹ̀ niti Maher-ṣalal-haṣ-basi. 2 Emi si mu awọn ẹlẹri otitọ sọdọ mi lati ṣe ẹlẹri. Uriah alufa, ati Sekariah ọmọ Jeberekiah. 3 Mo si wọle tọ wolĩ obinrin ni lọ; o si loyun o si bi ọmọkunrin kan. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, sọ orukọ rẹ̀ ni Maher-ṣalal-haṣ-basi. 4 Nitoripe ki ọmọ na to ni oye ati ke pe, Baba mi, ati iya mi, ọrọ̀ Damasku ati ikogun Samaria ni a o mu kuro niwaju ọba Assiria.

Ọba Asiria ń Bọ̀ Wá

5 Oluwa si tun wi fun mi pe, 6 Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah. 7 Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀. 8 Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli. 9 Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu. 10 Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.

OLUWA Kìlọ̀ fún Wolii

11 Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe, 12 Ẹ máṣe pè gbogbo eyi ni imulẹ ti awọn enia yi pè ni imulẹ: bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀ru ibẹ̀ru wọn, ẹ má si ṣe foya. 13 Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin. 14 On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu. 15 Ọ̀pọlọpọ ninu wọn yio si kọsẹ, nwọn o si ṣubu, a o si fọ wọn, a o si mu wọn.

Ìkìlọ̀ nípa Bíbá Òkú Sọ̀rọ̀

16 Di ẹri na, fi edídi di ofin na lãrin awọn ọmọ-ẹhin mi. 17 Emi o si duro de Oluwa, ti o pa oju rẹ̀ mọ kuro lara ile Jakobu, emi o si ma wo ọ̀na rẹ̀. 18 Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Oluwa ti fi fun mi wà fun àmi ati fun iyanu ni Israeli, lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti ngbe òke Sioni. 19 Nigbati nwọn ba si wi fun nyin pe, Ẹ wá awọn ti mba okú lò, ati awọn oṣó ti nke, ti nsi nkùn, kò ha yẹ ki orilẹ-ède ki o wá Ọlọrun wọn jù ki awọn alãye ma wá awọn okú? 20 Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni.

Àkókò Ìṣòro

21 Nwọn o si kọja lọ lãrin rẹ̀, ninu inilara ati ebi: yio si ṣe pe nigbati ebi yio pa wọn, nwọn o ma kanra, nwọn o si fi ọba ati Ọlọrun wọn re, nwọn o si ma wò òke. 22 Nwọn o si wò ilẹ, si kiyesi i, iyọnu ati okùnkun, iṣuju irora: a o si le wọn lọ sinu okùnkun.

Isaiah 9

Ọba Lọ́la

1 ṢUGBỌN iṣuju na kì yio wà nibiti wahalà mbẹ nisisiyi, gẹgẹ bi ìgba iṣãju ti mu itìju wá si ilẹ Sebuloni ati ilẹ Naftali, bẹ̃ni ìgba ikẹhin yio mu ọla wá si ọ̀na okun, niha ẹkùn Jordani, Galili awọn orilẹ-ède. 2 Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si. 3 Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun. 4 Nitori iwọ ṣẹ́ ajàga-irú rẹ̀, ati ọpá ejika rẹ̀, ọgọ aninilara rẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ Midiani. 5 Nitori gbogbo ihamọra awọn ologun ninu irọkẹ̀kẹ, ati aṣọ ti a yi ninu ẹ̀jẹ, yio jẹ fun ijoná ati igi iná. 6 Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia. 7 Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.

OLUWA yóo Jẹ Israẹli Níyà

8 Oluwa rán ọ̀rọ si Jakobu, o si ti bà lé Israeli. 9 Gbogbo enia yio si mọ̀ ọ, Efraimu ati awọn ti ngbe Samaria, ti nwi ninu igberaga, ati lile aiya pe, 10 Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn. 11 Nitorina li Oluwa yio gbe awọn aninilara Resini dide si i, yio si dá awọn ọtá rẹ̀ pọ̀. 12 Awọn ara Siria niwaju, ati awọn Filistini lẹhin: nwọn o si fi gbogbo ẹnu jẹ Israeli run. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ. 13 Awọn enia na kọ yipada si ẹniti o lù wọn, bẹ̃ni nwọn kò wá Oluwa awọn ọmọ-ogun. 14 Nitorina ni Oluwa yio ke ori ati irù, imọ̀-ọpẹ ati koriko-odo kuro ni Israeli, li ọjọ kan. 15 Agbà ati ọlọla, on li ori, ati wolĩ ti nkọni li eké, on ni irù. 16 Nitori awọn olori enia yi mu wọn ṣìna: awọn ti a si tọ́ li ọ̀na ninu wọn li a parun. 17 Nitorina ni Oluwa kì yio ṣe ni ayọ̀ ninu ọdọ-ọmọkunrin wọn, bẹ̃ni ki yio ṣãnu fun awọn alainibaba ati opo wọn: nitori olukuluku wọn jẹ agabagebe ati oluṣe-buburu, olukuluku ẹnu nsọ wère. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ. 18 Nitori ìwa-buburu njo bi iná: yio jo ẹwọn ati ẹgún run, yio si ràn ninu pàntiri igbó, nwọn o si goke lọ bi ẹ̃fin iti goke. 19 Nipa ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ fi ṣõkùn, awọn enia yio dabi igi iná, ẹnikan kì yio dá arakunrin rẹ̀ si. 20 On o si jajẹ li ọwọ́ ọ̀tun, ebi o si pa a; on o si jẹ li ọwọ́ osì; nwọn kì yio si yo: olukuluku enia yio si jẹ ẹran-ara apa rẹ̀. 21 Manasse o jẹ Efraimu; Efraimu o si jẹ Manasse: awọn mejeji o dojukọ Juda. Ni gbogbo eyi, ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.

Isaiah 10

1 EGBE ni fun awọn ti npaṣẹ aiṣododo, ati fun awọn akọwe ti nkọ iwe ìka; 2 Lati yi alaini kuro ni idajọ, ati lati mu ohun ẹtọ kuro lọwọ talakà enia mi, ki awọn opo ba le di ijẹ wọn, ati ki wọn ba le jà alainibaba li ole! 3 Kili ẹnyin o ṣe lọjọ ibẹ̀wo, ati ni idahoro ti yio ti okere wá? tali ẹnyin o sá tọ̀ fun irànlọwọ? nibo li ẹnyin o si fi ogo nyin si? 4 Laisi emi nwọn o tẹ̀ ba labẹ awọn ara-tubu, nwọn o si ṣubu labẹ awọn ti a pa. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.

Asiria ṣe Àṣejù

5 Egbe ni fun Assuri, ọgọ ibinu mi, ati ọ̀pa ọwọ́ wọn ni irúnu mi. 6 Emi o ran a si orilẹ-ède agabàgebe, ati fun awọn enia ibinu mi li emi o paṣẹ kan, lati ko ikogun, ati lati mu ohun ọdẹ, ati lati tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ni igboro. 7 Ṣugbọn on kò rò bẹ̃, bẹ̃ni ọkàn rẹ̀ kò rò bẹ̃; ṣugbọn o wà li ọkàn rẹ̀ lati parun ati lati ke orilẹ-ède kuro, ki iṣe diẹ. 8 Nitori o wipe, Ọba kọ awọn ọmọ-alade mi ha jẹ patapata? 9 Kalno kò ha dabi Karkemiṣi? Hamati kò ha dabi Arpadi? Samaria kò ha dabi Damasku? 10 Gẹgẹ bi ọwọ́ mi ti nà de ijọba ere ri, ere eyi ti o jù ti Jerusalemu ati ti Samaria lọ. 11 Bi emi ti ṣe si Samaria ati ere rẹ̀, emi kì yio ha ṣe bẹ̃ si Jerusalemu ati ere rẹ̀ bi? 12 Nitorina yio si ṣe, nigbati Oluwa ti ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀ lori òke Sioni ati Jerusalemu, emi o ba eso aiya lile ọba Assiria wi, ati ogo ìwo giga rẹ̀. 13 Nitori o wipe, nipa agbara ọwọ́ mi ni emi ti ṣe e, ati nipa ọgbọ́n mi; nitori emi moye, emi si ti mu àla awọn enia kuro, emi si ti ji iṣura wọn, emi si ti sọ awọn ará ilu na kalẹ bi alagbara ọkunrin. 14 Ọwọ́ mi si ti wá ọrọ̀ awọn enia ri bi itẹ ẹiyẹ: ati gẹgẹ bi ẹnipe ẹnikan nko ẹyin ti o kù, li emi ti kó gbogbo aiye jọ; kò si ẹniti o gbọ̀n iyẹ, tabi ti o ya ẹnu, tabi ti o dún. 15 Ãke ha le fọnnu si ẹniti nfi i la igi? tabi ayùn ha le gbe ara rẹ̀ ga si ẹniti nmì i? bi ẹnipe ọgọ le mì ara rẹ̀ si awọn ti o gbe e soke, tabi bi ẹnipe ọpa le gbe ara rẹ̀ soke, bi ẹnipe ki iṣe igi. 16 Nitorina ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio mu awọn tirẹ̀ ti o sanra di rirù: ati labẹ ogo rẹ̀ yio da jijo kan bi jijo iná. 17 Imọlẹ Israeli yio si jẹ iná, ati Ẹni-Mimọ́ rẹ̀ yio jẹ ọwọ́-iná: yio si jo ẹgún ati ẹwọn rẹ̀ run, li ọjọ kan; 18 Yio si jo ogo igbó rẹ̀ run, ati oko rẹ̀ ẹlẹtù loju, ati ọkàn ati ara: nwọn o si dabi igbati ọlọpagun ndakú. 19 Iyokù igi igbó rẹ̀ yio si jẹ diẹ, ti ọmọde yio le kọwe wọn.

Àwọn Díẹ̀ Yóo Pada Wá

20 Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ. 21 Awọn iyokù yio pada, awọn iyokù ti Jakobu, si Ọlọrun alagbara. 22 Bi Israeli enia rẹ ba dàbi iyanrìn okun, sibẹ iyokù ninu wọn o pada: aṣẹ iparun na yio kun àkúnwọ́sílẹ̀ ninu ododo. 23 Nitori Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe iparun, ani ipinnu, li ãrin ilẹ gbogbo.

OLUWA Yóo Jẹ Asiria Níyà

24 Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti. 25 Ṣugbọn niwọn igba diẹ kiun, irunú yio si tan, ati ibinu mi ninu iparun wọn. 26 Oluwa awọn ọmọ-ogun yio gbe paṣan kan soke fun u, gẹgẹ bi ipakupa ti Midiani ni apata Orebu: ati gẹgẹ bi ọgọ rẹ̀ soju okun, bẹ̃ni yio gbe e soke gẹgẹ bi iru ti Egipti. 27 Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbe ẹrù rẹ̀ kuro li ejika rẹ, ati àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ, a o si ba àjaga na jẹ ní ọrùn rẹ.

Ọ̀tá Kọlu Jerusalẹmu

28 On de si Aiati, on ti kọja si Migroni; ni Mikmaṣi li on ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ si: 29 Nwọn ti rekọja ọ̀na na: nwọn ti wọ̀ ni Geba; Rama bẹ̀ru; Gibea ti Saulu sá. 30 Gbe ohùn rẹ soke, ọmọbinrin Gallimu: mu ki a gbọ́ ọ de Laiṣi, otòṣi Anatoti. 31 A ṣi Madmena nipo dà; awọn ara Gebimu ko ara wọn jọ lati sa. 32 Yio duro sibẹ ni Nobu li ọjọ na: on o si mì ọwọ́ rẹ̀ si oke giga ọmọbinrin Sioni, oke kekere Jerusalemu. 33 Kiyesi i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio fi ẹ̀ru wọ́n ẹka: ati awọn ti o ga ni inà li a o ke kuro, ati awọn agberaga li a o rẹ̀ silẹ. 34 On o si fi irin ke pantiri igbó lu ilẹ, Lebanoni yio si ṣubu nipa alagbara kan.

Isaiah 11

Ìjọba Tí Ó Tòrò

1 ẼKÀN kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ̀: 2 Ẹmi Oluwa yio si bà le e, ẹmi ọgbọ́n ati oye, ẹmi igbimọ̀ ati agbara, ẹmi imọ̀ran ati ibẹ̀ru Oluwa. 3 Õrùn-didùn rẹ̀ si wà ni ibẹ̀ru Oluwa, on ki yio si dajọ nipa ìri oju rẹ̀, bẹ̃ni ki yio dajọ nipa gbigbọ́ eti rẹ̀; 4 Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa. 5 Ododo yio si jẹ amure ẹgbẹ́ rẹ̀, ati iṣotitọ amure inu rẹ̀. 6 Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ̀; ọmọ kekere yio si ma dà wọn. 7 Malũ ati beari yio si ma jẹ pọ̀; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ̀; kiniun yio si jẹ koriko bi malũ. 8 Ọmọ ẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pãmọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ́ rẹ̀ si ihò ejò. 9 Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun.

Àwọn Ìgbèkùn Yóo Pada

10 Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo. 11 Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ̀ lati gbà awọn enia rẹ̀ iyokù padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣi, ati lati Elamu, ati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá. 12 On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn aṣati Israeli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá. 13 Ilara Efraimu yio si tan kuro; Efraimu ki yio ṣe ilara Juda, Juda ki yio si bà Efraimu ninu jẹ. 14 Ṣugbọn nwọn o si fò mọ ejika awọn Filistini siha iwọ̀-õrun; nwọn o jùmọ bà awọn ti ilà-õrun jẹ: nwọn o si gbe ọwọ́ le Edomu ati Moabu; awọn ọmọ Ammoni yio si gbà wọn gbọ́. 15 Oluwa yio si pa ahọn okun Egipti run tũtũ; ẹfũfu lile rẹ̀ ni yio si mì ọwọ́ rẹ̀ lori odo na, yio si lù u ni iṣàn meje, yio si jẹ ki enia rekọja ni batà gbigbẹ. 16 Ọna opopo kan yio si wà fun iyokù awọn enia rẹ̀, ti yio kù, lati Assiria; gẹgẹ bi o ti ri fun Israeli li ọjọ ti o goke jade kuro ni ilẹ Egipti.

Isaiah 12

Orin Ọpẹ́

1 ATI li ọjọ na iwọ o si wipe, Oluwa, emi o yìn ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu. 2 Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹ̀ru: nitori Oluwa Jehofah li agbara mi ati orin mi; on pẹlu si di igbala mi. 3 Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá. 4 Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke. 5 Kọrin si Oluwa: nitori o ti ṣe ohun didara: eyi di mimọ̀ ni gbogbo aiye. 6 Kigbe, si hó, iwọ olugbe Sioni: nitori ẹni titobi ni Ẹni-Mimọ́ Israeli li ãrin rẹ.

Isaiah 13

Ọlọrun Yóo Jẹ Babiloni Níyà

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti Babiloni ti Isaiah ọmọ Amosi ri. 2 Ẹ gbe ọpágun soke lori oke giga, ẹ kọ si wọn, ẹ juwọ, ki nwọn ba le lọ sinu ẹnu-odi awọn ọlọla. 3 Emi ti paṣẹ fun awọn temi ti a yà si mimọ́, emi ti pe awọn alagbara mi pẹlu fun ibinu mi, ani awọn ti nwọn yọ̀ ninu ọlanla mi. 4 Ariwo ọ̀pọlọpọ lori oke, gẹgẹ bi ti enia pupọ̀: ariwo rudurudu ti ijọba awọn orilẹ-ède, ti a kojọ pọ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun gbá ogun awọn ọmọ-ogun jọ. 5 Nwọn ti ilẹ okerè wá, lati ipẹkun ọrun, ani, Oluwa, ati ohun-elò ibinu rẹ̀, lati pa gbogbo ilẹ run. 6 Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá. 7 Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́. 8 Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná. 9 Kiyesi i, ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, o ni ibi ti on ti ikannú ati ibinu gbigboná, lati sọ ilẹ na di ahoro: yio si pa awọn ẹlẹṣẹ run kuro ninu rẹ̀. 10 Nitori awọn iràwọ ọrun, ati iṣùpọ iràwọ inu rẹ̀ kì yio tàn imọlẹ wọn: õrun yio ṣu okùnkun ni ijadelọ rẹ̀, oṣùpa kì yio si mu ki imọlẹ rẹ̀ tàn. 11 Emi o si bẹ̀ ibi wò lara aiye, ati aiṣedẽde lara awọn enia buburu; emi o si mu ki igberaga awọn agberaga ki o mọ, emi o si mu igberaga awọn alagbara rẹ̀ silẹ. 12 Emi o mu ki ọkunrin kan ṣọwọ́n ju wura lọ; ani enia kan ju wura Ofiri daradara. 13 Nitorina emi o mu ọrun mì titi, ilẹ aiye yio si ṣipò rẹ̀ pada, ninu ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀. 14 Yio si dabi abo agbọ̀nrin ti a nlepa, ati bi agutan ti ẹnikan kò gbajọ: olukuluku wọn o yipada si enia rẹ̀, olukuluku yio si sa si ilẹ rẹ̀. 15 Ẹnikẹni ti a ri li a o gun li agunyọ; ẹnikẹni ti o si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wọn yio ti ipa idà ṣubu. 16 Ọmọ wọn pẹlu li a o fọ́ tũtu loju ara wọn; a o si kó wọn ni ile, a o si fi agbara bà obinrin wọn jẹ́; 17 Kiyesi i, emi o gbe awọn ara Media dide si wọn, ti ki yio ka fadakà si; bi o si ṣe ti wura, nwọn ki yio ni inu didùn si i. 18 Ọrun wọn pẹlu yio fọ́ awọn ọdọmọkunrin tũtũ; nwọn ki yio ṣãnu fun ọmọ-inu: oju wọn kì yio dá ọmọde si. 19 Ati Babiloni, ogo ijọba gbogbo, ẹwà ogo Kaldea, yio dabi igbati Ọlọrun bi Sodomu on Gomorra ṣubu. 20 A kì yio tẹ̀ ẹ dó mọ, bẹ̃ni a kì yio si gbe ibẹ̀ mọ lati irandiran: bẹ̃ni awọn ara Arabia kì yio pagọ nibẹ mọ; bẹ̃ni awọn oluṣọ-agutan kì yio kọ́ agbo wọn nibẹ mọ. 21 Ṣugbọn ẹranko igbẹ yio dubulẹ nibẹ; ile wọn yio si kun fun òwiwí, abo ogòngo yio ma gbe ibẹ, ọ̀rọ̀ yio si ma jo nibẹ. 22 Awọn ọ̀wawa yio si ma ke ninu ãfin wọn, ati dragoni ninu gbọ̀ngàn wọn daradara: ìgba rẹ̀ si sunmọ etile, a kì yio si fa ọjọ rẹ̀ gùn.

Isaiah 14

Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn

1 NITORI Oluwa yio ṣãnu fun Jakobu, yio si tun yan Israeli, yio si mu wọn gbe ilẹ wọn; alejò yio si dapọ̀ mọ wọn, nwọn o si faramọ ile Jakobu. 2 Awọn enia yio si mu wọn, nwọn o si mu wọn wá si ipò wọn: ile Israeli yio si ni wọn ni ilẹ Oluwa, fun iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin: awọn ti o ti kó wọn ni igbekun ni nwọn o kó ni igbekun; nwọn o si ṣe akoso aninilara wọn.

Ọba Babiloni ní Isà Òkú

3 Yio si ṣe li ọjọ ti Oluwa yio fun ọ ni isimi kuro ninu ibanujẹ rẹ, ati kuro ninu ijaiya rẹ, ati kuro ninu oko-ẹru lile nibiti a ti mu ọ sìn, 4 Ni iwọ o si fi ọba Babiloni ṣẹ̀fẹ yi, ti iwọ o si wipe, Aninilara nì ha ti ṣe dakẹ! alọnilọwọgbà wura dakẹ! 5 Oluwa ti ṣẹ ọpá oluṣe-buburu, ati ọpá-alade awọn alakoso. 6 Ẹniti o fi ibinu lù awọn enia lai dawọ duro, ẹniti o fi ibinu ṣe akoso awọn orilẹ-ède, li a nṣe inunibini si, lai dẹkun. 7 Gbogbo aiye simi, nwọn si gbe jẹ: nwọn bú jade ninu orin kikọ. 8 Nitõtọ, igi firi nyọ̀ ọ, ati igi kedari ti Lebanoni, wipe, Lati ìgba ti iwọ ti dubulẹ, kò si akegi ti o tọ̀ wa wá. 9 Ipò-okú lati isalẹ wá mì fun ọ lati pade rẹ li àbọ rẹ: o rú awọn okú dide fun ọ, ani gbogbo awọn alakoso aiye; o ti gbe gbogbo ọba awọn orilẹ-ède dide kuro lori itẹ wọn. 10 Gbogbo wọn o dahùn, nwọn o si wi fun ọ pe, Iwọ pẹlu ti di ailera gẹgẹ bi awa? iwọ ha dabi awa? 11 Ogo rẹ li ati sọ̀kalẹ si ipò-okú, ati ariwo durù rẹ: ekòlo ti tàn sabẹ rẹ, idin si bò ọ mọ ilẹ. 12 Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wá, Iwọ Lusiferi, iràwọ owurọ! bawo li a ti ṣe ke ọ lu ilẹ, iwọ ti o ti ṣẹ́ awọn orilẹ-ède li apa! 13 Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa: 14 Emi o goke kọja giga awọsanma: emi o dabi ọga-ogo jùlọ. 15 Ṣugbọn a o mu ọ sọkalẹ si ipò okú, si iha ihò. 16 Awọn ti o ri ọ yio tẹjumọ ọ, nwọn o si ronu rẹ pe, Eyi li ọkunrin na ti o mu aiye wárìrì, ti o mu ilẹ ọba mìtiti; 17 Ti o sọ aiye dàbi agìnju, ti o si pa ilu rẹ̀ run; ti kò dá awọn ondè rẹ̀ silẹ lati lọ ile? 18 Gbogbo ọba awọn orilẹ-ède, ani gbogbo wọn, dubulẹ ninu ogo, olukuluku ninu ile rẹ̀. 19 Ṣugbọn iwọ li a gbe sọnù kuro nibi iboji rẹ bi ẹka irira, bi aṣọ awọn ti a pa, awọn ti a fi idà gun li agunyọ, ti nsọkalẹ lọ si ihò okuta; bi okú ti a tẹ̀ mọlẹ. 20 A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai. 21 Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye.

Ọlọrun Yóo Pa Babiloni Run

22 Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi. 23 Emi o si ṣe e ni ilẹ-ini fun õrẹ̀, ati àbata omi; emi o si fi ọwọ̀ iparun gbá a, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Ọlọrun Yóo Pa Àwọn Ará Asiria Run

24 Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bura, wipe, Lõtọ gẹgẹ bi mo ti gberò, bẹ̃ni yio ri, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹ̃ni yio si duro: 25 Pe, emi o fọ́ awọn ara Assiria ni ilẹ mi, ati lori oke mi li emi o tẹ̀ ẹ mọlẹ labẹ ẹsẹ: nigbana li ajàga rẹ̀ yio kuro lara wọn, ati ẹrù rẹ̀ kuro li ejiká wọn. 26 Eyi ni ipinnu ti a pinnu lori gbogbo aiye: eyi si ni ọwọ́ ti a nà jade lori gbogbo orilẹ-ède. 27 Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pinnu, tani yio si sọ ọ di asan? ọwọ́ rẹ̀ si nà jade, tani yio si dá a padà?

Ọlọrun Yóo Pa Àwọn Ará Filistini Run

28 Li ọdun ti Ahasi ọba kú, li ọ̀rọ-imọ yi wà. 29 Iwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nitori paṣan ẹniti o nà ọ ṣẹ́; nitori lati inu gbòngbo ejo ni pãmọlẹ kan yio jade wá, irú rẹ̀ yio si jẹ́ ejò iná ti nfò. 30 Akọbi awọn otòṣi yio si jẹ, awọn alaini yio si dubulẹ lailewu; emi o si fi iyàn pa gbòngbo rẹ, on o si pa iyokù rẹ. 31 Hu, iwọ ẹnu-odi; kigbe, iwọ ilu; gbogbo Palestina, iwọ ti di yiyọ́: nitori ẹ̃fin yio ti ariwa jade wá, ẹnikan kì yio si yà ara rẹ̀ kuro lọdọ ẹgbẹ́ rẹ̀. 32 Èsi wo li a o fi fun awọn ikọ̀ orilẹ-ède? Pe, Oluwa ti tẹ̀ Sioni dó, talaka ninu awọn enia rẹ̀ yio si sá wọ̀ inu rẹ̀.

Isaiah 15

OLUWA yóo Pa Moabu Run

1 ỌRỌ-imọ̀ niti Moabu. Nitori li oru li a sọ Ari ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ; nitori li oru li a sọ Kiri ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ; 2 On ti goke lọ si Bajiti, ati si Diboni, ibi giga wọnni, lati sọkun: Moabu yio hu lori Nebo, ati lori Medeba: gbogbo ori wọn ni yio pá, irungbọ̀n olukulùku li a o fá. 3 Ni igboro ni wọn o da aṣọ-ọ̀fọ bò ara wọn: lori okè ilé wọn, ati ni igboro wọn, olukuluku yio hu, yio si ma sọkun pẹ̀rẹpẹ̀rẹ. 4 Heṣboni yio si kigbe, ati Eleale: a o si gbọ́ ohùn wọn titi dé Jahasi: nitorina ni awọn ọmọ-ogun Moabu ti o hamọra yio kigbe soke; ọkàn rẹ̀ yio bajẹ fun ara rẹ̀. 5 Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke. 6 Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si. 7 Nitorina ọ̀pọ eyi ti nwọn ti ni, ati eyi ti nwọn ti kojọ, ni nwọn o gbe kọja odò willo. 8 Nitori igbe na ti yi agbegbè Moabu ka; igbe na si de Eglaimu, ati igbe na de Beerelimu. 9 Nitori odò Dimoni yio kún fun ẹ̀jẹ: nitori emi o fi ibi miran sori Dimoni, emi o mu kiniun wá sori ẹniti ó sálà kuro ni Moabu, ati lori awọn ti o kù ni ilẹ na.

Isaiah 16

Kò sí Ìrètí fún Moabu Mọ́

1 Ẹ rán ọdọ-agutan si alakoso ilẹ lati Sela wá si aginju, si oke ọmọbinrin Sioni. 2 Yio si ṣe, bi alarinkiri ẹiyẹ ti a le jade kuro ninu itẹ́-ẹiyẹ, bẹ̃ni ọmọbinrin Moabu yio ri ni iwọdò Arnoni. 3 Ẹ gbìmọ, ẹ mu idajọ ṣẹ; ṣe ojiji rẹ bi oru li ãrin ọsángangan; pa awọn ti a le jade mọ́; máṣe fi isánsa hàn. 4 Moabu, jẹ ki awọn isánsa mi ba ọ gbe, iwọ ma jẹ ãbo fun wọn li oju akoni: nitori alọnilọwọgbà de opin, akoni dasẹ̀, a pa awọn aninilara run kuro lori ilẹ. 5 Ninu ãnu li a o si fi idi ilẹ mulẹ: yio si joko lori rẹ̀ li otitọ ninu agọ Dafidi, yio ma ṣe idajọ, yio si ma wá idajọ, yio si ma mu ododo yara kánkán. 6 Awa ti gbọ́ ti igberaga Moabu; o gberaga pọju: ani ti irera rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati ibinu rẹ̀; ihalẹ rẹ̀ asan ni. 7 Nitorina ni Moabu yio hu fun Moabu, gbogbo wọn o hu: nitori ipilẹ Kir-haresi li ẹnyin o gbàwẹ; nitõtọ a lù wọn. 8 Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun. 9 Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ. 10 A si mu inu-didun kuro, ati ayọ̀ kuro ninu oko ti nso eso ọ̀pọlọpọ; orin kì yio si si mọ ninu ọgbà-àjara, bẹ̃ni kì yio si ihó-ayọ̀ mọ: afọnti kì yio fọn ọti-waini mọ ninu ifọnti wọn, emi ti mu ariwo dá. 11 Nitorina inu mi yio dún bi harpu fun Moabu, ati ọkàn mi fun Kir-haresi. 12 Yio si ṣe, nigbati a ba ri pe ãrẹ̀ mú Moabu ni ibi giga, ni yio wá si ibi-mimọ́ rẹ̀ lati gbadura; ṣugbọn kì yio bori. 13 Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti Moabu lati igbà na wá. 14 Ṣugbọn nisisiyi Oluwa ti sọ̀rọ, wipe, Niwọn ọdun mẹta, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, a o si kẹgàn ogo Moabu, pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ nì: awọn iyokù yio kere, kì yio si li agbara.

Isaiah 17

Ọlọrun Yóo Jẹ Siria ati Israẹli Níyà

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti Damasku. Kiye si i, a mu Damasku kuro lati ma jẹ ilu, yi o si di òkiti àlapa. 2 A kọ̀ gbogbo ilu Aroeri silẹ: nwọn o jẹ ti ọ̀wọ-ẹran, ti yio dubulẹ, ẹnikẹni kì yio dẹrubà wọn. 3 Odi kì yio si si mọ ni Efraimu, ati ijọba ni Damasku, ati iyokù ti Siria: nwọn o dabi ogo awọn ọmọ Israeli, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 4 Li ọjọ na yio si ṣe, a o mu ogo Jakobu dinkù, ati sisanra ara rẹ̀ li a o sọ di rirù. 5 Yio si dabi igbati olukorè nkó agbado jọ, ti o si nfi apá rẹ̀ rẹ́ ipẹ́-ọkà yio si dabi ẹniti nkó ipẹ́-ọkà jọ ni afonifoji Refaimu. 6 Ṣugbọn ẽṣẹ́ eso-àjara yio hù ninu rẹ̀, gẹgẹ bi mimì igi olifi, eso kekere meji bi mẹta ni ṣonṣo oke ẹka mẹrin bi marun ni ẹka ode ti o ni eso pupọ, li Oluwa Ọlọrun Israeli wi. 7 Li ọjọ na li ẹnikan yio wò Ẹlẹda rẹ̀, ati oju rẹ̀ yio si bọ̀wọ fun Ẹni-Mimọ Israeli. 8 On kì yio si wò pẹpẹ, iṣẹ ọwọ́ rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si bọ̀wọ fun eyi ti ika rẹ̀ ti ṣe, yala igbo-òriṣa tabi ere-õrun. 9 Li ọjọ na ni ilu alagbara rẹ̀ yio dabi ẹka ìkọsilẹ, ati ẹka tente oke ti nwọn fi silẹ nitori awọn ọmọ Israeli: iparun yio si wà. 10 Nitori iwọ ti gbagbe Ọlọrun igbala rẹ, ti iwọ kò si nani apata agbára rẹ, nitorina ni iwọ ti gbìn ọ̀gbin daradara, iwọ si tọ́ àjeji ẹka sinu rẹ̀. 11 Li ọjọ na ni iwọ o mu ki ọ̀gbin rẹ dàgba, ati li owurọ ni iwọ o mu ki irugbin rẹ rú: ṣugbọn a o mu ikorè lọ li ọjọ ini, ikãnu kikoro yio si wà.

A Ṣẹgun Àwọn Ọ̀tá

12 Egbé ni fun ariwo ọ̀pọ enia, ti o pa ariwo bi ariwo okun; ati fun irọ́ awọn orilẹ-ède, ti nwọn rọ bi rirọ́ omi pupọ̀! 13 Awọn orilẹ-ède yio rọ́ bi rirọ́ omi pupọ: ṣugbọn Ọlọrun yio bá wọn wi, nwọn si sa jina rere, a o si lepa wọn gẹgẹ bi ìyangbo oke-nla niwaju ẹfũfu, ati gẹgẹ bi ohun yiyi niwaju ãjà. 14 Si kiye si i, li aṣalẹ, iyọnu; ki ilẹ to mọ́ on kò si. Eyi ni ipín awọn ti o kó wa, ati ipín awọn ti o jà wa li olè.

Isaiah 18

Ọlọrun yóo Jẹ Sudani Níyà

1 EGBE ni fun ilẹ ti o ni ojiji apá meji, ti o wà ni ikọja odò Etiopia: 2 Ti o rán awọn ikọ̀ li ọ̀na okun, ani ninu ọkọ̀ koriko odò, li oju odò, wipe, Lọ, ẹnyin onṣẹ ti o yara kánkan, si orilẹ-ède ti a nà ká ti a si tẹju, si enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá, ti o si tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà! 3 Gbogbo ẹnyin ti ngbe aiye, ati olugbé aiye, ẹ wò, nigbati on gbe ọpagun sori awọn oke giga; ati nigbati on fọn ipè, ẹ gbọ́. 4 Nitori bẹ̃li Oluwa sọ fun mi, emi o simi, emi o si gbèro ninu ibugbé mi, bi oru ọsángangan, ati bi awọsanma ìri, ninu oru ikorè. 5 Nitori ṣaju ikorè, nigbati ìrudi ba kún, ti itanná ba di eso-àjara pipọn on o fi dojé rẹ́ ẹka-titun, yio si mu kuro, yio si ke ẹka lu ilẹ. 6 A o si fi wọn silẹ fun awọn ẹiyẹ oke-nla, ati fun awọn ẹranko aiye: awọn ẹiyẹ yio yá õrùn lori wọn, gbogbo awọn ẹranko aiye yio si potutù lori wọn. 7 Li akoko na ni a o mu ọrẹ wá fun Oluwa awọn ọmọ-ogun lati ọdọ awọn enia ti a nà ka, ti a si tẹju, ati enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá ti o tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà, si ibi orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, oke giga Sioni.

Isaiah 19

Ọlọrun Yóo Jẹ Egipti Níyà

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti Egipti. Kiyesi i, Oluwa ngùn awọsanma ti o yara, yio si wá si Egipti: a o si ṣi ipò awọn òriṣa Egipti pàda niwaju rẹ̀, aiya Egipti yio yọ́ li ãrin rẹ̀. 2 Emi o si gbe Egipti dide si Egipti: olukuluku yio si ba arakunrin rẹ̀ jà, ati olukuluku aladugbò rẹ̀; ilu yio dojukọ ilu, ati ijọba yio dojukọ ijọba. 3 Ẹmi Egipti yio si rẹ̀wẹsi lãrin inu rẹ̀; emi o si pa ìmọ inu rẹ̀ run: nwọn o si wá a tọ̀ òriṣa lọ, ati sọdọ awọn atuju, ati sọdọ awọn ajẹ́, ati sọdọ awọn oṣó; 4 Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Awọn ara Egipti li emi o fi le oluwa onrorò li ọwọ́; ọba ti o muna yio ṣe akoso wọn. 5 Omi yio si buṣe li okun, a o si fi odò ṣofo, yio si gbẹ. 6 Odò yio si di rirùn; odò ãbo li a o sọ di ofo, ti a o si gbọ́n gbẹ; oko-odò ati iyè yio rọ. 7 Oko-tutù ni ipadò, li ẹnu odò, ati ohun gbogbo ti a gbìn sipadò, ni yio rọ, yio funka, kì yio si si mọ. 8 Awọn apẹja yio gbàwẹ pẹlu, ati gbogbo awọn ti nfì ìwọ li odò yio pohùnrére-ẹkun; ati awọn ti nda àwọn li odò yio sorikọ́. 9 Pẹlupẹlu awọn ti nṣiṣẹ ọ̀gbọ daradara, ati awọn ti nwun asọ-àla yio dãmu. 10 A o si fọ́ wọn ni ipilẹ rẹ̀, gbogbo awọn alagbàṣe li a o bà ni inu jẹ. 11 Nitõtọ òpe ni awọn ọmọ-alade Soani, ìmọ awọn ìgbimọ ọlọgbọn Farao di wère: ẹ ha ti ṣe sọ fun Farao, pe, Emi li ọmọ ọlọgbọn, ọmọ awọn ọba igbãni? 12 Awọn dà? awọn ọlọgbọn rẹ dà? si jẹ ki wọn sọ fun ọ nisisiyi, si jẹ ki wọn mọ̀ ete ti Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pa le Egipti. 13 Awọn ọmọ-alade Soani di aṣiwère, a tàn awọn ọmọ-alade Nofi jẹ; ani awọn ti iṣe pataki ẹyà rẹ̀. 14 Oluwa ti mí ẽmi iyapa si inu rẹ̀ na: nwọn si ti mu Egipti ṣina ninu gbogbo iṣẹ inu rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀muti enia ti nta gbọngbọ́n ninu ẽbi rẹ̀. 15 Bẹ̃ni kì yio si iṣẹkiṣẹ́ fun Egipti, ti ori tabi ìru, ẹka tabi oko-odò, le ṣe.

Egipti Yóo Sin OLUWA

16 Li ọjọ na ni Egipti yio dabi obinrin; yio si warìri, ẹ̀ru yio si bà a nitori mimì ọwọ́ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o mì le e lori. 17 Ilẹ Juda yio si di ẹ̀ru fun Egipti, olukuluku ẹniti o dá a sọ ninu rẹ̀ yio tikararẹ̀ bẹ̀ru, nitori ìmọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o ti gbà si i. 18 Li ọjọ na ni ilu marun ni ilẹ Egipti yio fọ̀ ède Kenaani, ti nwọn o sì bura si Oluwa awọn ọmọ-ogun; a o ma pè ọkan ni Ilu ìparun. 19 Li ọjọ na ni pẹpẹ kan yio wà fun Oluwa li ãrin ilẹ Egipti, ati ọwọ̀n ni àgbegbe inu rẹ̀ fun Oluwa. 20 Yio si jẹ fun ami, ati fun ẹ̀ri si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ Egipti: nitori nwọn o kigbe pè Oluwa nitori awọn aninilara, yio si rán olugbala kan si i, ati ẹni-nla, on o si gbà wọn. 21 Oluwa yio si di mimọ̀ fun Egipti, awọn ara Egipti yio so mọ́ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si rú ẹbọ, nwọn o si ta ọrẹ; nitõtọ nwọn o jẹ'jẹ fun Oluwa, nwọn o si mu u ṣẹ. 22 Oluwa o si lù Egipti bolẹ, yio si mu u li ara da: nwọn o si yipada si Oluwa, on o si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn, yio si mu wọn li ara da. 23 Li ọjọ na ni opopo kan yio wà lati Egipti de Assiria, awọn ara Assiria yio si wá si Egipti, awọn ara Egipti si Assiria, awọn ara Egipti yio si sìn pẹlu awọn ara Assiria. 24 Li ọjọ na ni Israeli yio jẹ ẹkẹta pẹlu Egipti ati pẹlu Assiria, ani ibukún li ãrin ilẹ na: 25 Ti Oluwa awọn ọmọ-ogun yio bukún fun, wipe, Ibukun ni fun Egipti enia mi, ati fun Assiria iṣẹ ọwọ́ mi, ati fun Israeli ini mi.

Isaiah 20

Àmì Wolii tó Wà Níhòohò

1 LI ọdun ti Tartani wá si Aṣdodi, (nigbati Sargoni ọba Assiria rán a,) ti o si ba Aṣdodi jà, ti o si kó o; 2 Li akoko na li Oluwa wi nipa Isaiah ọmọ Amosi, pe, Lọ, bọ aṣọ-ọ̀fọ kuro li ẹgbẹ́ rẹ, si bọ́ bàta rẹ kuro li ẹsẹ rẹ. O si ṣe bẹ̃, o nrin nihòho ati laibọ̀ bàta. 3 Oluwa si wipe, Gẹgẹ bi Isaiah iranṣẹ mi ti rìn nihòho ati laibọ̀ bàta li ọdun mẹta fun ami ati iyanu lori Egipti ati lori Etiopia; 4 Bẹ̃li ọba Assiria yio kó awọn ara Egipti ni igbèkun ati awọn ara Etiopia ni igbèkun, ọmọde ati arugbo, nihòho ati laibọ̀ bàta, ani ti awọn ti idí wọn nihòho, si itiju Egipti. 5 Ẹ̀ru yio si bà wọn, oju o si tì wọn fun Etiopia ireti wọn, ati fun Egipti ogo wọn. 6 Awọn olugbé àgbegbe okun yio si wi li ọjọ na pe, Kiyesi i, iru eyi ni ireti wa, nibiti awa salọ fun iranlọwọ ki a ba le gbani là kuro li ọwọ́ ọba Assiria: ati bawo li a o si ṣe salà?

Isaiah 21

Ìran nípa Ìṣubú Babiloni

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti ijù okun. Gẹgẹ bi ãja gusù ti ikọja lọ; bẹ̃ni o ti ijù wá, lati ilẹ ti o li ẹ̀ru. 2 Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da. 3 Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i. 4 Ọkàn mi nrò, ẹ̀ru dẹrùba mi: oru ayọ̀ mi li o ti sọ di ìbẹru fun mi. 5 Pèse tabili silẹ, yàn alore, jẹ, mu: dide, ẹnyin ọmọ-alade, ẹ kùn asà nyin. 6 Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, Lọ, fi ẹnikan ṣọ ọ̀na, jẹ ki o sọ ohun ti o ri. 7 O si ri kẹkẹ́ pẹlu ẹlẹṣin meji-meji, kẹkẹ́ kẹtẹkẹtẹ, kẹkẹ́ ibakasiẹ; o si farabalẹ̀ tẹtilelẹ gidigidi: 8 On si kigbe pe, kiniun kan: Oluwa mi, nigbagbogbo li emi nduro lori ile-iṣọ li ọsan, a si fi mi si iṣọ mi ni gbogbo oru: 9 Si kiyesi i, kẹkẹ́ enia kan ni mbọ̀ wá yi, pẹlu ẹlẹṣin meji-meji. On si dahun, o si wipe, Babiloni ṣubu, o ṣubu; ati gbogbo ere fifin òriṣa rẹ̀ li o wó mọlẹ. 10 Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu

11 Ọ̀rọ-ìmọ niti Duma. O ké si mi lati Seiri wá, Oluṣọ́, oru ti ri? Oluṣọ́ oru ti ri? 12 Oluṣọ́ wipe, ilẹ nmọ́ bọ̀, alẹ si nlẹ pẹlu: bi ẹnyin o ba bere, ẹ bere: ẹ pada, ẹ wá.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia

13 Ọ̀rọ-ìmọ niti Arabia. Ninu igbó Arabia li ẹnyin o wọ̀, ẹnyin ẹgbẹ́-erò Dedanimu. 14 Awọn olugbé ilẹ Tema bù omi wá fun ẹniti ongbẹ ngbẹ, onjẹ wọn ni nwọn fi ṣaju ẹniti nsalọ. 15 Nitori nwọn nsá fun idà, fun idà fifayọ, ati fun ọrun kikàn, ati fun ibinujẹ ogun. 16 Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, ki ọdun kan to pe, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, gbogbo ogo Kedari yio wọ̀. 17 Iyokù ninu iye awọn tafàtafà, awọn alagbara ninu awọn ọmọ Kedari yio dinkù: nitori Oluwa Ọlọrun Israeli ti wi i.

Isaiah 22

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti afonifoji ojuran. Kili o ṣe ọ nisisiyi, ti iwọ fi gùn ori ile lọ patapata? 2 Iwọ ti o kún fun ìrukerudo, ilu aitòro, ilu ayọ̀: a kò fi idà pa awọn okú rẹ, bẹ̃ni nwọn kò kú li ogun. 3 Gbogbo awọn alakoso rẹ ti jumọ sa lọ, awọn tafàtafà ti dì wọn ni igbekun: gbogbo awọn ti a ri ninu rẹ li a dì jọ, ti o ti sa lati okere wá. 4 Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi. 5 Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla. 6 Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ. 7 Yio si ṣe, afonifoji àṣayan rẹ yio kún fun kẹkẹ́, awọn ẹlẹṣin yio si tẹ́ ogun niha ẹnu odi. 8 On si ri iboju Juda, iwọ si wò li ọjọ na ihamọra ile igbó. 9 Ẹnyin ti ri oju-iho ilu Dafidi pẹlu, pe, nwọn pọ̀: ẹnyin si gbá omi ikudu isalẹ jọ. 10 Ẹnyin ti kà iye ile Jerusalemu, awọn ile na li ẹnyin biwó lati mu odi le. 11 Ẹnyin pẹlu ti wà yàra lãrin odi meji fun omi ikudu atijọ: ṣugbọn ẹnyin kò wò ẹniti o ṣe e, bẹ̃ni ẹ kò si buyìn fun ẹniti o ṣe e nigbãni, 12 Ati li ọjọ na ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio pè lati sọkun, ati lati ṣọ̀fọ, ati lati fá ori, ati lati sán aṣọ ọ̀fọ. 13 Si kiyesi i, ayọ̀ ati inu-didùn, pipa malũ, ati pipa agutan, jijẹ ẹran, ati mimu ọti-waini: ẹ jẹ ki a ma jẹ, ki a si ma mu; nitori ọla li awa o kú. 14 Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ li eti mi, pe, Nitõtọ, a kì yio fọ̀ aiṣedede yi kuro lara nyin titi ẹnyin o fi kú, li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Ìkìlọ̀ fún Ṣebna

15 Bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Lọ, tọ olutọju yi lọ, ani tọ Ṣebna lọ, ti iṣe olori ile, 16 Si wipe, Kili o ni nihin? ati tali o ni nihin, ti iwọ fi wà ibojì nihin bi ẹniti o wà ibojì fun ara rẹ̀ nibi giga, ti o si gbẹ́ ibugbé fun ara rẹ̀ ninu apáta? 17 Kiyesi i, Oluwa yio fi sisọ agbara sọ ọ nù, yio si bò ọ mọlẹ. 18 Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ. 19 Emi o si le ọ jade kuro ni ibujoko rẹ, yio tilẹ wọ́ ọ kuro ni ipò rẹ. 20 Yio si ṣe li ọjọ na, ni emi o pè Eliakimu iranṣẹ mi ọmọ Hilkiah. 21 Emi o si fi aṣọ-igunwà rẹ wọ̀ ọ, emi o si fi àmure rẹ dì i, emi o si fi ijọba rẹ le e li ọwọ́: on o si jẹ baba fun awọn olugbé Jerusalemu, ati fun ile Juda. 22 Iṣikà ile Dafidi li emi o fi le èjiká rẹ̀: yio si ṣí, kò si ẹniti yio tì; on o si tì, kò si si ẹniti yio ṣí. 23 Emi o si kàn a bi iṣó ni ibi ti o le, on o jẹ fun itẹ ogo fun ile baba rẹ̀. 24 Gbogbo ogo ile baba rẹ̀ ni nwọn o si fi kọ́ ọ li ọrùn, ati ọmọ ati eso, gbogbo ohun-elò ife titi de ago ọti. 25 Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Li ọjọ na, ni a o ṣi iṣó ti a kàn mọ ibi ti o le ni ipò, a o si ke e lu ilẹ, yio si ṣubu; ẹrù ara rẹ̀ li a o ké kuro: nitori Oluwa ti sọ ọ.

Isaiah 23

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti Tire. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi; nitoriti a o sọ ọ di ahoro, tobẹ̃ ti kò si ile, kò si ibi wiwọ̀: a fi hàn fun wọn lati ilẹ Kittimu. 2 Ẹ duro jẹ, ẹnyin olugbé erekùṣu; iwọ ẹniti awọn oniṣowo Sidoni, ti nre okun kọja ti kún. 3 Ati nipa omi nla iru Sihori, ikorè odò, ni owo ọdun rẹ̀; on ni ọjà awọn orilẹ-ède. 4 Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba. 5 Gẹgẹ bi ihìn niti Egipti, bẹ̃ni ara yio ro wọn goro ni ihìn Tire. 6 Ẹ kọja si Tarṣiṣi; hu, ẹnyin olugbé erekùṣu. 7 Eyi ha ni ilu ayọ̀ fun nyin, ti o ti wà lati ọjọ jọjọ? ẹsẹ on tikara rẹ̀ yio rù u lọ si ọna jijìn rére lati ṣe atipó. 8 Tali o ti gbìmọ yi si Tire, ilu ade, awọn oniṣòwo ẹniti o jẹ ọmọ-alade, awọn alajapá ẹniti o jẹ ọlọla aiye? 9 Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pete rẹ̀, lati sọ irera gbogbo ogo di aimọ́, lati sọ gbogbo awọn ọlọla aiye di ẹ̀gan. 10 La ilẹ rẹ ja bi odò, iwọ ọmọbinrin Tarṣiṣi: àmure kò si mọ́. 11 O nà ọwọ́ rẹ̀ jade si oju okun, o mì awọn ijọba: Oluwa ti pa aṣẹ niti Kenaani, lati run agbàra inu rẹ̀. 12 On si wipe, Iwọ kò gbọdọ yọ̀ mọ, iwọ wundia ti a ni lara, ọmọbinrin Sidoni; dide rekọja lọ si Kittimu, nibẹ pẹlu iwọ kì yio ri isimi. 13 Wò ilẹ awọn ara Kaldea; awọn enia yi kò ti si ri, titi awọn ara Assiria tẹ̀ ẹ dó fun awọn ti ngbe aginju: nwọn kọ́ ile-iṣọ́ inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ãfin inu rẹ̀; on si pa a run. 14 Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi: nitori a sọ agbara nyin di ahoro. 15 Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbagbe Tire li ãdọrin ọdun, gẹgẹ bi ọjọ ọba kan: lẹhin ãdọrin ọdun ni Tire yio kọrin bi panṣaga obinrin. 16 Mu harpu kan, kiri ilu lọ, iwọ panṣaga obinrin ti a ti gbagbe; dá orin didùn: kọ orin pupọ̀ ki a le ranti rẹ. 17 Yio si ṣe li ẹhìn ãdọrin ọdun, ni Oluwa yio bẹ̀ Tire wò, yio si yipadà si ọ̀ya rẹ̀, yio si ba gbogbo ijọba aiye yi ti o wà lori ilẹ ṣe àgbere. 18 Ọjà rẹ̀ ati ọ̀ya rẹ̀ yio jẹ mimọ́ si Oluwa: a kì yio fi ṣura, bẹ̃li a ki yio tò o jọ; nitori ọjà rẹ̀ yio jẹ ti awọn ti ngbe iwaju Oluwa, lati jẹ ajẹtẹrùn, ati fun aṣọ daradara.

Isaiah 24

OLUWA Yóo Jẹ Ilẹ̀ Ayé Níyà

1 KIYESI i, Oluwa sọ aiye di ofo, o si sọ ọ di ahoro, o si yi i po, o si tú awọn olugbé inu rẹ̀ ka. 2 Yio si ṣe, bi o ti ri fun awọn enia, bẹ̃li o ri fun alufa; bi o ti ri fun iranṣẹ-kunrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun iranṣẹbinrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun olùra, bẹ̃ni fun olùta; bi o ti ri fun awinni, bẹ̃ni fun atọrọ; bi o ti ri fun agbà elé, bẹ̃ni fun ẹniti o san ele fun u. 3 Ilẹ yio di ofo patapata, yio si bajẹ patapata: nitori Oluwa ti sọ ọ̀rọ yi. 4 Ilẹ̀ nṣọ̀fọ o si nṣá, aiye nrù o si nṣá, awọn ẹni giga ilẹ njoro. 5 Ilẹ pẹlu si di aimọ́ li abẹ awọn ti ngbe inu rẹ̀; nitori nwọn ti rú ofin, nwọn pa ilàna dà, nwọn dà majẹmu aiyeraiye. 6 Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rẹ̀ di ahoro: nitorina ni awọn ti ngbe ilẹ jona, enia diẹ li o si kù. 7 Ọti-waini titun nṣọ̀fọ, àjara njoro, gbogbo awọn ti nṣe aríya nkẹdùn. 8 Ayọ̀ tabreti dá, ariwo awọn ti nyọ̀ pin, ayọ̀ harpu dá. 9 Nwọn kì yio fi orin mu ọti-waini mọ́; ọti-lile yio koro fun awọn ti nmu u. 10 A wó ilu rúdurudu palẹ: olukuluku ile li a se, ki ẹnikan má bà wọle. 11 Igbe fun ọti-waini mbẹ ni igboro; gbogbo ayọ̀ ṣú òkunkun, aríya ilẹ na lọ. 12 Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode. 13 Nigbati yio ri bayi li ãrin ilẹ lãrin enia na, bi mimì igi olifi, ati bi pipẽṣẹ eso-àjara nigbati ikorè àjara tán. 14 Nwọn o gbe ohùn wọn soke, nwọn o kọrin nitori ọla-nla Oluwa, nwọn o kigbe kikan lati okun wá. 15 Nitorina yìn Oluwa li ogo ni ilẹ imọlẹ, ani orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli li erekùṣu okun. 16 Lati opin ilẹ li awa ti gbọ́ orin, ani ogo fun olododo. Ṣugbọn emi wipe, Iparun mi, iparun mi, egbé ni fun mi! awọn ọ̀dalẹ ti dalẹ: nitõtọ, awọn ọ̀dalẹ dalẹ rekọja. 17 Ibẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati ẹgẹ́, wà lori rẹ, iwọ ti ngbe ilẹ-aiye. 18 Yio si ṣe, ẹniti o sá kuro fun ariwo ìbẹru yio jin sinu ọ̀fin; ati ẹniti o jade lati inu ọ̀fin wá li a o fi ẹgẹ́ mu: nitori awọn ferese lati oke wá ṣi silẹ, ipilẹ ilẹ si mì. 19 Ilẹ di fifọ́ patapata, ilẹ di yíyọ patapata, ilẹ mì tìtì. 20 Ilẹ yio ta gbọ̀ngbọn sihin sọhun bi ọ̀mutí, a o si ṣi i ni idí bi agọ́; irekọja inu rẹ̀ yio wọ̀ ọ li ọrùn; yio si ṣubu, kì yio si dide mọ́. 21 Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio bẹ̀ ogun awọn ẹni-giga ni ibi-giga wò, ati awọn ọba aiye li aiye. 22 A o si ko wọn jọ pọ̀, bi a iti kó ara tubu jọ sinu ihò, a o tì wọn sinu tubu, lẹhin ọjọ pupọ̀ li a o si bẹ̀ wọn wò. 23 Nigbana li a o dãmu oṣupa, oju yio si tì õrun, nigbati Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jọba li oke Sioni, ati ni Jerusalemu, ogo yio si wà niwaju awọn alàgba rẹ̀.

Isaiah 25

Orin Ìyìn

1 OLUWA, iwọ li Ọlọrun mi; emi o gbe ọ ga, emi o yìn orukọ rẹ; nitori iwọ ti ṣe ohun iyanu; ìmọ igbani, ododo ati otitọ ni. 2 Nitori iwọ ti sọ ilu kan di okiti; iwọ ti sọ ilu olodi di iparun: ãfin awọn alejo, kò jẹ ilu mọ́; a kì yio kọ́ ọ mọ. 3 Nitorina ni awọn alagbara enia yio yìn ọ li ogo, ilu orilẹ-ède ti o ni ibẹ̀ru yio bẹ̀ru rẹ. 4 Nitori iwọ ti jẹ agbara fun talaka, agbara fun alaini ninu iṣẹ́ rẹ̀, ãbo kuro ninu ìji, ojiji kuro ninu oru, nigbati ẹfũfu lile awọn ti o ni ibẹ̀ru dabi ìji lara ogiri. 5 Iwọ o mu ariwo awọn alejo rọlẹ, gẹgẹ bi oru nibi gbigbẹ; ani oru pẹlu ojiji awọsanma: a o si rẹ̀ orin-ayọ̀ awọn ti o ni ibẹ̀ru silẹ.

Ọlọrun se Àsè Ńlá

6 Ati ni oke-nla yi li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sè asè ohun abọ́pa fun gbogbo orilẹ-ède, asè ọti-waini lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ, ti ohun abọpa ti o kún fun ọra, ti ọti-waini ti o tòro lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ. 7 Li oke-nla yi on o si pa iboju ti o bò gbogbo enia loju run, ati iboju ti a nà bò gbogbo orilẹ-ède. 8 On o gbe iku mì lailai; Oluwa Jehofah yio nù omije nù kuro li oju gbogbo enia; yio si mu ẹ̀gan enia rẹ̀ kuro ni gbogbo aiye: nitori Oluwa ti wi i. 9 A o si sọ li ọjọ na pe, Wò o, Ọlọrun wa li eyi; awa ti duro de e, on o si gbà wa là: Oluwa li eyi: awa ti duro de e, awa o ma yọ̀, inu wa o si ma dùn ninu igbala rẹ̀.

Ọlọrun Yóo Jẹ Moabu Níyà

10 Nitori li oke-nla yi ni ọwọ́ Oluwa yio simi, yio si tẹ Moabu labẹ rẹ̀, ani gẹgẹ bi ãti tẹ̀ koriko mọlẹ fun ãtan. 11 Yio si nà ọwọ́ rẹ̀ jade li ãrin wọn, gẹgẹ bi òmùwẹ̀ iti nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati wẹ̀: on o si rẹ̀ igberaga wọn silẹ pọ̀ pẹlu ikogun ọwọ́ wọn. 12 Odi alagbara, odi giga, odi rẹ li on o wó lulẹ, yio rẹ̀ ẹ silẹ, yio mu u wá ilẹ, ani sinu ekuru.

Isaiah 26

Orin Ìgbàlà

1 LI ọjọ na li a o kọ orin yi ni ilẹ Juda; Awa ní ilu agbara; igbala li Ọlọrun yio yàn fun odi ati ãbo. 2 Ẹ ṣi ilẹkun bodè silẹ, ki orilẹ-ède ododo ti nṣọ́ otitọ ba le wọ̀ ile. 3 Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ. 4 Ẹ gbẹkẹle Oluwa titi lai: nitori Oluwa Jehofa li apata aiyeraiye: 5 Nitori o rẹ̀ awọn ti ngbe oke giga silẹ; ilu giga, o mu u wálẹ; o mu u wálẹ; ani si ilẹ; o mu u de inu ekuru. 6 Ẹsẹ yio tẹ̀ ẹ mọlẹ, ani ẹsẹ awọn talaka, ati ìṣísẹ̀ awọn alaini. 7 Ọ̀na awọn olõtọ ododo ni: iwọ, olõtọ-julọ, ti wọ̀n ipa-ọ̀na awọn olõtọ. 8 Nitõtọ, Oluwa, li ọ̀na idajọ rẹ, li awa duro de ọ: ifẹ́ ọkàn wa ni si orukọ rẹ, ati si iranti rẹ. 9 Ọkàn mi li emi fi ṣe afẹ̃ri rẹ li oru; nitõtọ, pẹlu ẹmi mi ninu mi li emi o wá ọ ni kutùkutù; nitori nigbati idajọ rẹ mbẹ ni ilẹ, awọn ti mbẹ li aiye yio kọ́ ododo. 10 Bi a ba fi ojurere hàn enia buburu, kì yio kọ́ ododo: ni ilẹ iduroṣinṣin li on o hùwa aiṣõtọ, kì yio si ri ọlanla Oluwa. 11 Oluwa, ọwọ́ rẹ gbe soke, nwọn kì yio ri, ṣugbọn nwọn o ri, oju o si tì wọn nitori ilara wọn si awọn enia; nitõtọ, iná awọn ọta rẹ yio jẹ wọn run. 12 Oluwa, iwọ o fi idi alafia mulẹ fun wa: pẹlupẹlu nitori iwọ li o ti ṣe gbogbo iṣẹ wa fun wa. 13 Oluwa Ọlọrun wa, awọn oluwa miran lẹhin rẹ ti jọba lori wa: ṣugbọn nipa rẹ nikan li awa o da orukọ rẹ sọ. 14 Awọn okú, nwọn kì yio yè; awọn ti ngbe isà-okú, nwọn kì yio dide; nitorina ni iwọ ṣe bẹ̀ wọn wò ti o si pa wọn run, ti o si mu ki gbogbo iranti wọn parun. 15 Iwọ ti mu orilẹ-ède bi si i, Oluwa, iwọ ti mu orilẹ-ède bi si i; iwọ ti di ẹni-ãyin li ogo: iwọ ti sún gbogbo ãlà siwaju. 16 Oluwa, ninu wahala ni nwọn wá ọ, nwọn gbadura wúyẹ́wúyẹ́ nigbati ibawi rẹ wà lara wọn. 17 Gẹgẹ bi aboyun, ti o sunmọ akoko ibi rẹ̀, ti wà ni irora, ti o si kigbe ninu irora rẹ̀; bẹ̃li awa ti wà li oju rẹ, Oluwa. 18 Awa ti loyun, awa ti wà ni irora, o si dabi ẹnipe awa ti bi ẹfũfu; awa kò ṣiṣẹ igbala kan lori ilẹ, bẹ̃ni awọn ti ngbe aiye kò ṣubu. 19 Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebẹ̀ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade.

Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò

20 Wá, enia mi, wọ̀ inu iyẹ̀wu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣẹ́ju kan, titi ibinu na fi rekọja. 21 Nitorina, kiye si i, Oluwa ti ipò rẹ̀ jade lati bẹ̀ aiṣedede ẹniti ngbe ori ilẹ wo lori ilẹ; ilẹ pẹlu yio fi ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn, kì yio si bo okú rẹ̀ mọ.

Isaiah 27

1 LI ọjọ na li Oluwa yio fi idà rẹ̀ mimú ti o tobi, ti o si wuwo bá lefiatani ejò ti nfò wi, ati lefiatani ejò wiwọ́ nì; on o si pa dragoni ti mbẹ li okun. 2 Li ọjọ na ẹ kọrin si i, Ajàra ọti-waini pipọ́n. 3 Emi Oluwa li o ṣọ ọ: emi o bù omi wọ́n ọ nigbakugba: ki ẹnikẹni má ba bà a jẹ, emi o ṣọ ọ ti oru ti ọsan. 4 Irunú kò si ninu mi: tani le doju pantiri ẹlẹgun ati ẹgun kọ mi li ogun jijà? emi iba là wọn kọja, emi iba fi wọn jona pọ̀ ṣọ̀kan. 5 Tabi jẹ ki o di agbara mi mu, ki o ba le ba mi lajà; yio si ba mi lajà. 6 Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye. 7 On ha lù u bi o ti nlu awọn ti o lù u? a ha pa a gẹgẹ bi pipa awọn ti on pa? 8 Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun. 9 Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro. 10 Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run. 11 Nigbati ẹka inu rẹ̀ ba rọ, a o ya wọn kuro: awọn obinrin de, nwọn si tẹ̀ iná bọ̀ wọn: nitori alaini oye enia ni nwọn: nitorina ẹniti o dá wọn kì yio ṣãnu fun wọn, ẹniti o si mọ wọn kì yio fi ojurere hàn wọn. 12 Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli. 13 Yio si ṣe li ọjọ na, a o fun ipè nla, awọn ti o mura lati ṣegbe ni ilẹ Assiria yio si wá, ati awọn aṣátì ilẹ Egipti, nwọn o si sìn Oluwa ni oke mimọ́ ni Jerusalemu.

Isaiah 28

Ìkìlọ̀ fún Ilẹ̀ Israẹli

1 EGBE ni fun ade igberaga, fun awọn ọmuti Efraimu, ati fun itàna rirọ ti ogo ẹwà rẹ̀, ti o wà lori afonifoji ọlọra ti awọn ti ọti-waini pa. 2 Kiye si i, Oluwa ni ẹnikan alagbara ati onipá, bi ẹfũfu lile, yiyin, ati ìji iparun, bi iṣàn-omi nla àkúnya, yio fi ọwọ́ bì ṣubu sori ilẹ. 3 Ade igberaga, awọn ọmuti Efraimu, li a o fi ẹsẹ tẹ̀ mọlẹ: 4 Ati ogo ẹwà, ti o wà lori afonifoji ọlọra, yio jẹ itanna rirọ, gẹgẹ bi eso ti o yara ṣaju igba ìkore; eyiti nigbati ẹniti o ba nwò o ba ri, nigbati o wà li ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbe e mì. 5 Li ọjọ na li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jẹ ade ogo, ati ade ẹwà fun iyokù awọn enia rẹ̀, 6 Ati ẹmi idajọ fun awọn ẹniti o joko ni idajọ, ati agbara fun awọn ti o le ogun padà si ibode.

Aisaya ati Àwọn Ọ̀mùtí Wolii Ilẹ̀ Juda

7 Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ. 8 Nitori gbogbo tabili li o kún fun ẽbi ati ẹgbin, kò si ibi ti o mọ́. 9 Tani on o kọ́ ni ìmọ? ati tani on o fi oye ẹkọ́ yé? awọn ẹniti a wọ́n li ẹnu-ọmú, ti a si já li ẹnu ọyàn. 10 Nitori aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ; ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: 11 Nitori nipa ète ẹlẹyà ati ni ède miran li on o fi bá enia wọnyi sọ̀rọ. 12 Si ẹniti on wipe, Eyi ni isimi, ẹnyin ìba mu awọn alãrẹ̀ simi; eyi si ni itura: sibẹ nwọn kì yio gbọ́. 13 Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn.

Òkúta Igun Ilé fún Sioni

14 Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ẹlẹgàn, ti nṣe akoso awọn enia yi ti mbẹ ni Jerusalemu. 15 Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ: 16 Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá. 17 Idajọ li emi o fi le ẹsẹ pẹlu, ati ododo li emi o fi lé òṣuwọn: yinyín yio gbá ãbo eke lọ, omi o si kún bò ibi isasi mọlẹ. 18 Majẹmu nyin ti ẹ ba ikú dá li a o sọ di asan, imulẹ nyin pẹlu ipò-okú kì yio duro; nigbati paṣán gigun yio rekọja; nigbana ni on o tẹ̀ nyin mọlẹ. 19 Niwọn igbati o ba jade lọ ni yio mu nyin: nitori ni gbogbo owurọ ni yio rekọja, li ọsan ati li oru: kiki igburo rẹ̀ yio si di ijaiyà. 20 Nitori akete kuru jù eyiti enia le nà ara rẹ̀ si, ati ìbora kò ni ibò to eyi ti on le fi bò ara rẹ̀. 21 Nitori Oluwa yio dide bi ti oke Perasimu, yio si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibeoni, ki o ba le ṣe iṣẹ rẹ̀, iṣẹ àrà rẹ̀; yio si mu iṣe rẹ̀ ṣẹ, ajeji iṣe rẹ̀. 22 Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ẹlẹgàn, ki a má ba sọ ìde nyin di lile; nitori emi ti gbọ́ iparun lati ọdọ Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti o ti pinnu lori gbogbo ilẹ.

Ọgbọ́n Ọlọrun

23 Ẹ fetisilẹ, ẹ si gbọ́ ohùn mi: ẹ tẹtilelẹ, ẹ si gbọ́ ọ̀rọ mi. 24 Gbogbo ọjọ ni agbẹ̀ ha nroko lati gbìn? on o ha ma tú, a si ma fọ́ ilẹ rẹ̀ bi? 25 Nigbati on ti tẹ́ ojú rẹ̀ tan, on kò ha nfunrugbìn dili, ki o si fọn irugbìn kummini ka, ki o si gbìn alikama lẹsẹ-ẹsẹ, ati barle ti a yàn, ati spelti nipò rẹ̀? 26 Nitori Ọlọrun rẹ̀ kọ́ ọ lati ni oye, o tilẹ kọ́ ọ. 27 Nitori a kò fi ohun-elò pakà dili, bẹ̃ni a kì iyí kẹkẹ́ kiri lori kummini; ṣugbọn ọpá li a ifi pa dili jade, ọgọ li a si fi lù kummini. 28 Akara agbado li a lọ̀; on kò le ma pa a titi, bẹ̃ni kò fi kẹkẹ́-ẹrù fọ́ ọ, bẹ̃ni kì ifi awọn ẹlẹṣin rẹ̀ tẹ̀ ẹ. 29 Eyi pẹlu ti ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ẹniti o kún fun iyanu ni ìmọ, ti o tayọ ni iṣe.

Isaiah 29

Òkè Sioni Ìlú Dafidi

1 EGBE ni fun Arieli, fun Arieli, ilu ti Dafidi ti ngbe! ẹ fi ọdun kún ọdun; jẹ ki wọn pa ẹran rubọ. 2 Ṣugbọn emi o pọ́n Arieli loju, àwẹ on ibanujẹ yio si wà; yio si dabi Arieli si mi. 3 Emi o si dótì ọ yika, emi o si wà odi tì ọ, emi o si mọ odi giga tì ọ. 4 A o si rẹ̀ ọ silẹ, iwọ o sọ̀rọ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio rẹ̀lẹ lati inu ekuru wá, ohùn rẹ yio si dabi ti ẹnikan ti o li ẹmi àfọṣẹ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio si dún lati inu erupẹ ilẹ wá. 5 Ọpọlọpọ awọn ọtá rẹ yio dabi ekuru lẹ́bulẹ́bu, ọpọlọpọ aninilara rẹ yio dabi ìyangbo ti o kọja lọ: lõtọ, yio ri bẹ̃ nisisiyi lojiji. 6 Ãrá, ìṣẹlẹ, ati iró nla, pẹlu ìji on ẹfúfu, ati ọwọ́ ajonirun iná ni a o fi bẹ̀ ọ wò lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá. 7 Bi alá iran oru li ọ̀pọlọpọ awọn orilẹ-ède ti mba Arieli jà yio ri; gbogbo ẹniti o bá ati on, ati odi agbara rẹ̀ jà, ti nwọn si pọ́n ọ loju. 8 Yio si dabi igbati ẹni ebi npa nla alá; si wo o, o njẹun; ṣugbọn o ji, ọkàn rẹ̀ si ṣofo: tabi bi igbati ẹniti ongbẹ ngbẹ nla alá, si wo o, o nmu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, ongbẹ si ngbẹ ọkàn rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio ri, ti mba oke Sioni jà.

Ìkìlọ̀ tí A kò Náání

9 Mu ara duro jẹ, ki ẹnu ki o yà nyin; ẹ fọ́ ara nyin loju, ẹ si fọju: nwọn mu amupara; ṣugbọn kì iṣe fun ọti-waini, nwọn nta gbọngbọ́n ṣugbọn kì iṣe fun ohun mimu lile. 10 Nitori Oluwa dà ẹmi õrun ijìka lù nyin, o si se nyin li oju: awọn wolĩ ati awọn olori awọn ariran nyin li o bò li oju. 11 Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i. 12 A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe. 13 Nitorina Oluwa wipe, Niwọ̀n bi awọn enia yi ti nfi ẹnu wọn fà mọ mi, ti nwọn si nfi etè wọn yìn mi, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìna si mi, ti nwọn si bẹru mi nipa ilana enia ti a kọ́ wọn. 14 Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra. 15 Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?

Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la

16 A, iyipo nyin! a ha le kà amọ̀koko si bi amọ̀: ohun ti a mọ ti ṣe lè wi fun ẹniti o ṣe e pe, On kò ṣe mi? ìkoko ti a mọ le wi fun ẹniti o mọ ọ pe, On kò moye? 17 Kò ha ṣe pe ìgba diẹ kiun si i, a o sọ Lebanoni di ọgbà eleso, ati ọgbà eleso li a o kà si bi igbo? 18 Ati li ọjọ na awọn aditi yio si gbọ́ ọ̀rọ iwe nì, awọn afọju yio si riran lati inu owúsuwusù, ati lati inu okunkun. 19 Ayọ̀ awọn onirẹlẹ yio bí si i ninu Oluwa, ati inu awọn talaka ninu awọn enia yio si dùn ninu Ẹni-Mimọ Israeli. 20 Nitori a sọ aninilara na di asan, a si pa ẹlẹgàn run, a si ké gbogbo awọn ti nṣọ́ aiṣedede kuro. 21 Ẹniti o dá enia li ẹbi nitori ọ̀rọ kan, ti nwọn dẹkùn silẹ fun ẹniti o baniwi ni ẹnubodè, ti nwọn si tì olododo si apakan, si ibi ofo. 22 Nitorina bayi li Oluwa, ẹniti o rà Abrahamu padà wi, pe, niti ile Jakobu, oju kì yio tì Jakobu mọ bẹ̃ni oju rẹ̀ kì yio yipada mọ. 23 Ṣugbọn nigbati on nri awọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, li ãrin rẹ̀, nwọn o yà orukọ mi si mimọ́, nwọn o si yà Ẹni-Mimọ Jakobu nì si mimọ́, nwọn o si bẹ̀ru Ọlọrun Israeli. 24 Awọn pẹlu ti o ṣinà nipa ẹmi, oye yio wá yé wọn, ati awọn ti nsọ bótibòti yio kọ́ ẹkọ́.

Isaiah 30

Àdéhùn tí kò Wúlò pẹlu Egipti

1 OLUWA wipe, egbé ni fun awọn ọlọ̀tẹ ọmọ, ti nwọn gbà ìmọ, ṣugbọn kì iṣe ati ọdọ mi; ti nwọn si mulẹ, ṣugbọn kì iṣe nipa ẹmi mi, ki nwọn ba le fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ: 2 Ti nwọn nrìn lọ si Egipti, ṣugbọn ti nwọn kò bere li ẹnu mi; lati mu ara wọn le nipa agbara Farao, ati lati gbẹkẹle ojiji Egipti! 3 Nitorina ni agbara Farao yio ṣe jẹ itiju nyin, ati igbẹkẹle ojiji Egipti yio jẹ idãmu nyin. 4 Nitori awọn olori rẹ̀ wá ni Soani, awọn ikọ̀ rẹ̀ de Hanesi. 5 Oju awọn enia kan ti kò li ère fun wọn tilẹ tì wọn, ti kò le ṣe iranwọ, tabi anfani, bikoṣe itiju ati ẹ̀gan pẹlu.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Àwọn ẹranko Ilẹ̀ Nẹgẹbu

6 Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère. 7 Egipti yio ṣe iranwọ lasan, kò si ni lari: nitorina ni mo ṣe kigbe pè e ni, Rahabu ti o joko jẹ.

Àwọn Aláìgbọràn

8 Nisisiyi lọ, kọ ọ niwaju wọn si walã kan, si kọ ọ sinu iwe kan, ki o le jẹ fun igbà ti mbọ lai ati lailai: 9 Pe, ọlọ̀tẹ enia ni awọn wọnyi, awọn ọmọ eké, awọn ọmọ ti kò fẹ igbọ́ ofin Oluwa: 10 Ti nwọn wi fun awọn ariran pe, Máṣe riran; ati fun awọn wolĩ pe, Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ́ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ̀ itanjẹ. 11 Kuro li ọna na, yẹ̀ kuro ni ipa na, mu ki Ẹni-Mimọ Israeli ki o dẹkun kuro niwaju wa. 12 Nitorina bayi li Ẹni-Mimọ Israeli wi, Nitoriti ẹnyin gàn ọ̀rọ yi, ti ẹnyin si gbẹkẹle ininilara on ìyapa, ti ẹnyin si gbe ara nyin lé e; 13 Nitorina ni aiṣedede yi yio ri si nyin bi odi yiya ti o mura ati ṣubu, ti o tiri sode lara ogiri giga, eyiti wiwó rẹ̀ de lojijì, lojukanna. 14 Yio si fọ́ ọ bi fifọ́ ohun-èlo amọ̀ ti a fọ́ tútu; ti a kò dasi: tobẹ̃ ti a kì yio ri apãdi kan ninu ẹfọ́ rẹ̀ lati fi fọ̀n iná li oju ãro, tabi lati fi bù omi ninu ikũdu. 15 Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ. 16 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bẹ̃kọ; nitori ẹṣin li a o fi sá; nitorina li ẹnyin o ṣe sá: ati pe, Awa o gùn eyi ti o lè sare; nitorina awọn ti yio lepa nyin yio lè sare. 17 Ẹgbẹrun yio sá ni ibawi ẹnikan; ni ibawi ẹni marun li ẹnyin o sá: titi ẹnyin o fi kù bi àmi lori oke-nla, ati bi asia lori oke. 18 Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e.

Ọlọrun Yóo Bukun Àwọn Eniyan Rẹ̀

19 Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn. 20 Oluwa yio si fi onjẹ ipọnju, ati omi inira fun nyin, awọn olukọ́ni rẹ kì yio sápamọ́ mọ, ṣugbọn oju rẹ yio ri olukọ́ni rẹ̀: 21 Eti rẹ o si gbọ́ ọ̀rọ kan lẹhin rẹ, wipe, Eyiyi li ọ̀na, ẹ ma rin ninu rẹ̀, nigbati ẹnyin bá yi si apa ọtún, tabi nigbati ẹnyin bá yi si apa òsi. 22 Ẹnyin o si sọ ibora ere fadaka nyin wọnni di aimọ́, ati ọṣọ́ ere wura didà nyin wọnni: iwọ o sọ wọn nù bi ohun-aimọ́, iwọ o si wi fun u pe, Kuro nihinyi. 23 On o si rọ̀ òjo si irugbin rẹ ti iwọ ti fọ́n si ilẹ: ati onjẹ ibísi ilẹ, yio li ọrá yio si pọ̀: li ọjọ na ni awọn ẹran rẹ yio ma jẹ̀ ni pápa oko nla. 24 Awọn akọ-malu pẹlu, ati awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ ti ntulẹ yio jẹ oko didùn, ti a ti fi kọ̀nkọsọ ati atẹ fẹ. 25 Ati lori gbogbo oke-nla giga, ati lori gbogbo oke kékèké ti o ga, ni odò ati ipa-omi yio wà li ọjọ pipa nla, nigbati ile-iṣọ́ wọnni bá wó. 26 Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn.

Ọlọrun Yóo Jẹ Asiria níyà

27 Kiyesi i, orukọ Ọluwa mbọ̀ lati ọ̀na jijin wá, ibinu rẹ̀ si njo, ẹrù rẹ̀ si wuwo: ète rẹ̀ si kún fun ikannu, ati ahọn rẹ̀ bi ajonirun iná: 28 Ẽmi rẹ̀ bi kikun omi, yio si de ãrin-meji ọrùn, lati fi kọ̀nkọsọ kù awọn orilẹ-ède: ijanu yio si wà li ẹ̀rẹkẹ́ awọn enia, lati mu wọn ṣina. 29 Ẹnyin o li orin kan, gẹgẹ bi igbati a nṣe ajọ li oru; ati didùn inu, bi igbati ẹnikan fun fère lọ, lati wá si òke-nla Oluwa, sọdọ Apata Israeli. 30 Oluwa yio si mu ki a gbọ́ ohùn ogo rẹ̀, yio si fi isọkalẹ apá rẹ̀ hàn pẹlu ikannu ibinu rẹ̀, ati pẹlu ọwọ́ ajonirun iná, pẹlu ifúnka, ati ijì, ati yinyín. 31 Nitori nipa ohùn Oluwa li a o fi lù awọn ara Assiria bo ilẹ, ti o fi kùmọ lù. 32 Ati nibi gbogbo ti paṣán ti a yàn ba kọja si, ti Oluwa yio fi lé e, yio ṣe pẹlu tabreti ati dùru: yio si fi irọ́kẹ̀kẹ ogun bá a jà. 33 Nitori a ti yàn Tofeti lati igbà atijọ; nitõtọ, ọba li a ti pèse rẹ̀ fun; o ti ṣe e ki o jìn, ki o si gbòro: okiti rẹ̀ ni iná ati igi pupọ; emi Oluwa, bi iṣàn imí-ọjọ́ ntàn iná ràn a.

Isaiah 31

Ọlọrun Yóo Dáàbò Bo Jerusalẹmu

1 EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa! 2 Ṣugbọn on gbọ́n pẹlu, o si mu ibi wá, kì yio si dá ọ̀rọ rẹ̀ padà: on si dide si ile awọn oluṣe buburu, ati si oluranlọwọ awọn ti nṣiṣẹ aiṣedede. 3 Nitori enia li awọn ara Egipti, nwọn kì iṣe Ọlọrun; ẹran li awọn ẹṣin wọn, nwọn kì si iṣe ẹmi. Oluwa yio si nà ọwọ́ rẹ̀, ki ẹniti nràn ni lọwọ ba le ṣubu, ati ki ẹniti a nràn lọwọ ba lè ṣubu, gbogbo wọn o jùmọ ṣegbe. 4 Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀. 5 Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti fi iyẹ́ apa ṣe, bẹ̃ni Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dabòbo Jerusalemu; ni didãbòbo o pẹlu yio si gbà o silẹ; ni rirekọja on o si dá a si. 6 Ẹ yipadà si ẹniti ẹ ti nṣọ̀tẹ si gidigidi, ẹnyin ọmọ Israeli. 7 Nitori li ọjọ na ni olukuluku enia yio jù ere fadaka rẹ̀, ati ere wura rẹ̀ nù, ti ọwọ́ ẹnyin tikara nyin ti ṣe fun ẹ̀ṣẹ fun nyin. 8 Nigbana ni ara Assiria na yio ṣubú nipa idà, ti kì iṣe nipa idà ọkunrin, ati idà, ti ki iṣe ti enia yio jẹ ẹ: ṣugbọn on o sá kuro niwaju idà, awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ma sìnrú. 9 Apata rẹ̀ yio kọja lọ fun ẹ̀ru, awọn olori rẹ̀ yiọ bẹ̀ru asia na, ni Oluwa wi, ẹniti iná rẹ̀ wà ni Sioni, ati ileru rẹ̀ ni Jerusalemu.

Isaiah 32

Ọba tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé

1 KIYESI i, ọba kan yio jẹ li ododo, awọn olori yio fi idajọ ṣe akoso. 2 Ẹnikan yio si jẹ bi ibi isápamọ́ kuro loju ẹfũfu, ati ãbo kuro lọwọ ijì; bi odo-omi ni ibi gbigbẹ, bi ojiji apata nla ni ilẹ gbigbẹ. 3 Oju awọn ẹniti o riran kì yio ṣe baibai, ati eti awọn ti o ngbọ́ yio tẹ́ silẹ. 4 Ọkàn awọn oniwàduwàdu yio mọ̀ oye, ahọn awọn akolòlo yio sọ̀rọ kedere. 5 A kì yio tun pè alaigbọ́n ni ẹni-ọlá mọ, bẹ̃ni a kì yio pe ọ̀bàlújẹ́ ni ẹni pataki mọ. 6 Nitori eniakenia yio ma sọ isọkusọ, ọkàn rẹ̀ yio si ma ṣiṣẹ aiṣedede, lati ṣe agabàgebe, ati lati ṣì ọ̀rọ sọ si Oluwa, lati sọ ọkàn ẹniti ebi npa di ofo, ati lati mu ki ohun-mimu awọn ti ongbẹ ngbẹ ki o dá. 7 Ibi ni gbogbo ohun-elò enia-kenia jẹ pẹlu: on gbà èro buburu, lati fi ọ̀rọ eke pa talaka run, bi alaini tilẹ nsọ õtọ ọ̀rọ. 8 Ṣugbọn ẹni-rere a ma gbèro ohun rere; nipa ohun-rere ni yio ṣe duro.

Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò

9 Dide, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; gbọ́ ohùn mi, ẹnyin alafara obinrin; fetisi ọ̀rọ mi. 10 Ọpọlọpọ ọjọ, on ọdún, li a o fi ma wahala nyin, ẹnyin alafara obinrin: nitori ikore kì yio si, kikojọ rẹ̀ kì yio de. 11 Warìri, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; ki wahala ba nyin ẹnyin alafara: ẹ tú aṣọ, ki ẹ si wà ni ihòho, ki ẹ si dì àmure ẹgbẹ́ nyin. 12 Nwọn o pohùnrere fun ọmú, fun pápa daradara, ati fun àjara eleso. 13 Ẹgún ọ̀gan on òṣuṣu yio wá sori ilẹ awọn enia mi; nitõtọ, si gbogbo ile ayọ̀ ni ilu alayọ̀. 14 Nitoripe a o kọ̀ ãfin wọnni silẹ; a o fi ilu ariwo na silẹ; odi ati ile-iṣọ́ ni yio di ihò titi lai, ayọ̀ fun kẹtẹkẹ́tẹ-igbẹ, pápa-oko fun ọwọ́-ẹran; 15 Titi a o fi tú Ẹmi jade si wa lara lati oke wá, ati ti aginju yio fi di ilẹ eléso, ti a o si kà ilẹ eleso si bi igbo. 16 Nigbana ni idajọ yio ma gbe aginju; ati ododo ninu ilẹ eleso. 17 Iṣẹ ododo yio si jẹ alafia, ati eso ododo yio jẹ idakẹjẹ on ãbo titi lai. 18 Awọn enia mi yio si ma gbe ibugbe alafia, ati ni ibugbe idaniloju, ati ni ibi isimi iparọrọ; 19 Ṣugbọn yio rọ̀ yìnyín, nigbati igbó nṣubu lulẹ; ati ni irẹlẹ a o rẹ̀ ilu na silẹ. 20 Alabukun fun ni ẹnyin ti nfọ̀nrugbìn niha omi gbogbo, ti nrán ẹṣẹ malu ati ti kẹtẹkẹtẹ jade sibẹ.

Isaiah 33

Adura fún Ìrànlọ́wọ́

1 EGBÉ ni fun iwọ abanijẹ, ti a kò si bà ọ jẹ: ti o nhùwa arekereke, ti a kò si hùwa arekereke si ọ! nigbati iwọ o dẹkun ati banijẹ, a o bà ọ jẹ; ati nigbati iwọ bá fi opin si ihùwa arekereke, nwọn o hùwa arekereke si ọ. 2 Oluwa, ṣãnu fun wa; awa ti duro dè ọ: iwọ mã ṣe apá wọn li òròwúrọ̀ ani igbala wa nigba ipọnju. 3 Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká. 4 A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn. 5 Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni. 6 On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀. 7 Kiyesi i, awọn akọni kigbe lode, awọn ikọ̀ alafia sọkún kikorò. 8 Ọ̀na opopo nla wọnni ṣófo, èro dá, on ti bà majẹmu jẹ, o ti kẹgàn ilu wọnni, kò kà ẹnikan si. 9 Ilẹ ngbawẹ̀ o si njoro, oju ntì Lebanoni o si rọ: Ṣaroni dabi aginju; ati Baṣani ati Karmeli gbọ̀n eso wọn danù.

OLUWA Kìlọ̀ fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀

10 Oluwa wipe, nisisiyi li emi o dide, nisisiyi li emi o gbe ara mi soke. 11 Ẹ o loyun iyangbò, ẹ o si bi pòropóro; ẽmi nyin, bi iná, yio jẹ nyin run. 12 Awọn enia yio si dabi sisun ẽru, bi ẹgún ti a ké ni nwọn o jo ninu iná. 13 Ẹ gbọ́, ẹnyin ti o jìna rére, eyi ti mo ti ṣe; ati ẹnyin ti o sunmọ tosí, ẹ jẹwọ agbara mi. 14 Ẹ̀ru bà awọn ẹlẹṣẹ̀ ni Sioni; ibẹru-bojo ti mu awọn agabàgebè. Tani ninu wa ti o le gbe inu ajonirun iná? tani ninu wa ti yio le gbe inu iná ainipẹkun? 15 Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi. 16 On na yio gbe ibi giga: ile apáta yio ṣe ibi ãbo rẹ̀: a o fi onjẹ fun u; omi rẹ̀ yio si daju.

Ọjọ́ Ọ̀la tó Lógo

17 Oju rẹ̀ yio ri ọba ninu ẹwà rẹ̀: nwọn o ma wò ilẹ ti o jina réré. 18 Aiyà rẹ yio ṣe aṣaro ẹ̀ru nla. Nibo ni akọwe wà? nibo ni ẹniti nwọ̀n nkan gbe wà? nibo ni ẹniti o nkà ile-ẹ̀ṣọ wọnni gbe wà? 19 Iwọ kì yio ri awọn enia ti o muná; awọn enia ti ọ̀rọ wọn jinlẹ jù eyiti iwọ le gbọ́, ti ahọn wọn ṣe ololò, ti kò le ye ọ. 20 Wo Sioni, ilu ajọ afiyesi wa: oju rẹ yio ri Jerusalemu ibugbe idakẹjẹ, agọ́ ti a kì yio tú palẹ mọ; kò si ọkan ninu ẽkàn rẹ ti a o ṣí ni ipò lai, bẹ̃ni kì yio si ọkan ninu okùn rẹ̀ ti yio já. 21 Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja. 22 Nitori Oluwa ni onidajọ wa, Oluwa li olofin wa, Oluwa li ọba wa; on o gbà wa là. 23 Okùn opó-ọkọ̀ rẹ tú; nwọn kò le dì opó-ọkọ̀ mu le danin-danin, nwọn kò le ta igbokun: nigbana li a pin ikogun nla; amúkun ko ikogun. 24 Ati awọn ará ibẹ̀ ki yio wipe, Ara mi kò yá: a o dari aiṣedede awọn enia ti ngbe ibẹ jì wọn.

Isaiah 34

Ọlọrun Yóo Jẹ Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ níyà

1 SUNMỌ tosí, ẹnyin orilẹ-ède lati gbọ́, tẹtisilẹ ẹnyin enia, jẹ ki aiye gbọ́, ati ẹ̀kun rẹ̀; aiye ati ohun gbogbo ti o ti inu rẹ̀ jade. 2 Nitori ibinu Oluwa mbẹ lara gbogbo orilẹ-ède, ati irúnu rẹ̀ lori gbogbo ogun wọn: o ti pa wọn run patapata, o ti fi wọn fun pipa. 3 Awọn ti a pa ninu wọn li a o si jù sode, õrùn wọn yio ti inu okú wọn jade, awọn oke-nla yio si yọ́ nipa ẹ̀jẹ wọn. 4 Gbogbo awọn ogun ọrun ni yio di yiyọ́, a o si ká awọn ọrun jọ bi takàda, gbogbo ogun wọn yio si ṣubu lulẹ, bi ewe ti ibọ́ kuro lara àjara, ati bi bibọ́ eso lara igi ọ̀pọtọ́. 5 Nitori ti a rẹ́ idà mi li ọrun, kiyesi i, yio sọkalẹ wá sori Idumea, ati sori awọn enia egún mi, fun idajọ. 6 Idà Oluwa kun fun ẹ̀jẹ, a mu u sanra fun ọ̀ra, ati fun ẹ̀jẹ ọdọ-agutan ati ewurẹ, fun ọrá erẽ àgbo: nitoriti Oluwa ni irubọ kan ni Bosra, ati ipakupa nla kan ni ilẹ Idumea. 7 Ati awọn agbanrere yio bá wọn sọkalẹ wá, ati awọn ẹgbọ̀rọ malu pẹlu awọn akọ malu; ilẹ wọn li a o fi ẹ̀jẹ rin, a o si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ra. 8 Nitori ọjọ ẹsan Oluwa ni, ati ọdun isanpadà, nitori ọ̀ran Sioni. 9 Odò rẹ̀ li a o si sọ di ọ̀dà, ati ekuru rẹ̀ di imi-õrun, ilẹ rẹ̀ yio si di ọ̀dà ti njona. 10 A kì o pa a li oru tabi li ọsan; ẹ̃fin rẹ̀ yio goke lailai: yio dahoro lati iran de iran; kò si ẹnikan ti yio là a kọja lai ati lailai. 11 Ṣugbọn ẹiyẹ ofú ati àkala ni yio ni i; ati owiwi ati iwò ni yio ma gbe inu rẹ̀: on o si nà okùn iparun sori rẹ̀, ati okuta ofo. 12 Niti awọn ijoye rẹ̀ ẹnikan kì yio si nibẹ ti nwọn o pè wá si ijọba, gbogbo awọn olori rẹ̀ yio si di asan. 13 Ẹgún yio si hù jade ninu ãfin rẹ̀ wọnni, ẹgún ọ̀gan ninu ilú olodi rẹ̀: yio jẹ ibugbé awọn dragoni, ati agbalá fun awọn owiwi. 14 Awọn ẹran ijù ati awọn ọ̀wawa ni yio pade, ati satire kan yio ma kọ si ekeji rẹ̀; iwin yio ma gbe ibẹ̀ pẹlu, yio si ri ibí isimi fun ara rẹ̀. 15 Owiwi yio tẹ́ itẹ́ rẹ̀ sibẹ̀, yio yé, yio si pa, yio si kojọ labẹ ojiji rẹ̀: awọn gúnugú yio pejọ sibẹ pẹlu, olukuluku pẹlu ẹnikeji rẹ̀. 16 Ẹ wá a ninu iwe Oluwa, ẹ si kà a: ọkan ninu wọnyi kì yio yẹ̀, kò si ọkan ti yio fẹ́ ekeji rẹ̀ kù: nitori ẹnu mi on li o ti paṣẹ, ẹmi rẹ̀ li o ti ko wọn jọ. 17 On ti dì ìbo fun wọn, ọwọ́ rẹ̀ si fi tita okùn pin i fun wọn: nwọn o jogun rẹ̀ lailai, lati iran de iran ni nwọn o ma gbe inu rẹ̀.

Isaiah 35

Ọ̀nà Ìwà Mímọ́

1 AGINJU ati ilẹ gbigbẹ yio yọ̀ fun wọn; ijù yio yọ̀, yio si tanna bi lili. 2 Ni titanna yio tanna; yio si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni li a o fi fun u, ẹwà Karmeli on Ṣaroni; nwọn o ri ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa. 3 Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun. 4 Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin. 5 Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi. 6 Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù. 7 Ilẹ yíyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi; ni ibugbé awọn dragoni, nibiti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ ọgbà fun ẽsú on iyè. 8 Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i. 9 Kiniun kì yio si nibẹ, bẹ̃ni ẹranko buburu kì yio gùn u, a kì yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rìn nibẹ: 10 Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.

Isaiah 36

Àwọn Ará Asiria Halẹ̀ mọ́ Jerusalẹmu

1 O si di igbati o ṣe li ọdun ikẹrinla Hesekiah ọba, Sennakeribu ọba Assiria wá dótì gbogbo ilu olodi Juda, o si kó wọn. 2 Ọba Assiria si rán Rabṣake lati Lakiṣi lọ si Jerusalemu, ti on ti ogun nla, sọdọ Hesekiah ọba. O si duro lẹba idari omi abàta oke, li opopo pápa afọṣọ. 3 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkia, olùtọ́ju ile, jade tọ̀ ọ wá, pẹlu Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu, akọwe iranti. 4 Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ wi fun Hesekiah nisisiyi, pe, Bayi li ọba nla, ọba Assiria wi, pe, Igbẹkẹle wo ni eyi ti iwọ gbe ara le yi? 5 Iwọ wi pe, Mo ni, (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn) emi ni ìmọ ati agbara fun ogun jija: njẹ tani iwọ tilẹ gbẹkẹle ti iwọ fi nṣọ̀tẹ si mi? 6 Wò o, iwọ gbẹkẹle ọpá iyè fifọ́ yi, le Egipti; eyiti bi ẹnikẹni ba fi ara tì, yio wọnu ọwọ́ rẹ̀, yio si gún u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri si gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. 7 Ṣugbọn bi iwọ ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on kọ́ ẹniti Hesekiah ti mu ibi giga rẹ̀ wọnni, ati pẹpẹ rẹ̀, wọnni kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi? 8 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun-iyàn wá fun oluwa mi ọba Assiria, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba le ni enia to lati gùn wọn. 9 Njẹ iwọ o ti ṣe le yi oju balogun kan pada ninu awọn ti o rẹhin jù ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si ngbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́, ati fun ẹlẹṣin? 10 Emi ha dá goke wá nisisiyi lẹhin Oluwa si ilẹ yi lati pa a run bi? Oluwa wi fun mi pe, Goke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run. 11 Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi. 12 Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin? 13 Nigbana ni Rabṣake duro, o si fi ohùn rara kigbe li ède awọn Ju, o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria. 14 Bayi ni ọba na wi, pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori on kì o lè gbà nyin. 15 Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a ki o fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ. 16 Ẹ máṣe fetisi ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Ẹ fi ẹ̀bun bá mi rẹ́, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá: ki olukuluku nyin ma jẹ ninu àjara rẹ̀, ati olukuluku nyin ninu igi ọ̀pọtọ́ rẹ̀, ki olukuluku nyin si ma mu omi ninu àmu on tikalarẹ̀; 17 Titi emi o fi wá lati mu nyin lọ si ilẹ kan bi ilẹ ẹnyin tikala nyin, ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọ̀gba àjara. 18 Ẹ ṣọra ki Hesekiah ki o má pa nyin niyè dà wipe, Oluwa yio gbà wa, ọkan ninu òriṣa awọn orilẹ-ède ha gba ilẹ rẹ̀ lọwọ ọba Assiria ri bi? 19 Nibo li awọn òriṣa Hamati on Arfardi gbe wà? Nibo li awọn òriṣa Sefarfaimu wà? nwọn ha si ti gbà Samaria li ọwọ́ mi bi? 20 Tani ninu gbogbo oriṣa ilẹ wọnyi, ti o ti gbà ilẹ wọn kuro li ọwọ́ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro li ọwọ́ mi? 21 Ṣugbọn nwọn dakẹ, nwọn kò si da a lohùn ọ̀rọ kan: nitoriti aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a lohùn. 22 Nigbana ni Eliakimu, ọmọ Hilkia, ti iṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa, ọmọ Asafu akọwe iranti, wá sọdọ Hesekiah ti awọn ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.

Isaiah 37

Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Isaiah

1 O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bora, o si lọ sinu ile Oluwa. 2 O si ran Eliakimu, ti o ṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn agba alufa ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bora, sọdọ Isaiah woli, ọmọ Amosi. 3 Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Oni jẹ ọjọ wahalà, ati ibawi, ati ẹgàn: nitori awọn ọmọ de igbà ibí, agbara kò si si lati bí wọn. 4 Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ ọ̀rọ Rabṣake, ẹniti oluwa rẹ̀ ọba Assiria ti rán lati gàn Ọlọrun alãyè, yio si ba ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́ wi: nitorina gbe adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù. 5 Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah. 6 Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ wi fun oluwa nyin, pe, Bayi ni Oluwa wi, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ ti iwọ ti gbọ́, nipa eyiti awọn iranṣẹ ọba Assiria ti fi sọ̀rọ buburu si mi. 7 Wò o, emi o fi ẽmi kan sinu rẹ̀, on o si gbọ́ iró kan, yio si pada si ilu on tikalarẹ̀; emi o si mu ki o ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.

Àwọn Ará Asiria Tún Halẹ̀ Lẹẹkeji

8 Bẹ̃ni Rabṣake padà, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitori ti o ti gbọ́ pe o ti kuro ni Lakiṣi. 9 O si gbọ́ a nwi niti Tirhaka ọba Etiopia, pe, O mbọ̀ wá ba iwọ jagun. Nigbati o si gbọ́, o rán awọn ikọ̀ lọ sọdọ Hesekiah, wipe, 10 Bayi ni ki ẹ wi fun Hesekiah ọba Juda, pe, Má jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle, ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọba Assiria lọwọ. 11 Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si ilẹ gbogbo bi nwọn ti pa wọn run patapata: a o si gbà iwọ bi? 12 Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun bi? bi Gosani, ati Harani ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti nwọn ti wà ni Telassari? 13 Nibo ni ọba Hamati wà, ati ọba Arfadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, Hena, ati Ifa?

Adura Hesekiah

14 Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn ikọ̀, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ si ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa. 15 Hesekiah si gbadura si Oluwa, wipe, 16 Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikan, ninu gbogbo ijọba aiye: iwọ li o dá ọrun on aiye. 17 Dẹti rẹ silẹ, Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Senakeribu, ti o ranṣẹ lati kẹgàn Ọlọrun alãyè. 18 Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti sọ gbogbo orilẹ-ède di ahoro, ati ilẹ wọn, 19 Nwọn si ti sọ awọn òriṣa wọn sinu iná: nitori ọlọrun ki nwọn iṣe, ṣugbọn iṣẹ ọwọ́ enia ni, igi ati òkuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run. 20 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ijọba aiye le mọ̀ pe iwọ ni Oluwa, ani iwọ nikanṣoṣo.

Aisaya Ranṣẹ Pada sí Ọba

21 Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah, wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niwọ̀n bi iwọ ti gbadura si mi niti Sennakeribu ọba Assiria: 22 Eyi ni ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀: Wundia, ọmọbinrin Sioni, ti kẹ́gàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ. 23 Tani iwọ kẹgàn ti o si sọ̀rọ buburu si? tani iwọ si gbe oju rẹ ga si, ti o si gbe oju rẹ soke gangan? si Ẹni-Mimọ́ Israeli ni. 24 Nipasẹ awọn iranṣẹ rẹ li o ti kẹgàn Oluwa, ti o si ti wipe, Ni ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ mi, emi ti goke wá si oke awọn oke giga, si ẹba Lebanoni; emi o si ke igi kedari rẹ̀ giga lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀, emi o si wá si ẹnu agbègbe rẹ̀, ati si igbó Karmeli rẹ̀. 25 Emi ti wà kanga, mo si ti mu omi; atẹlẹsẹ mi ni mo si ti fi mu gbogbo odò ibi ihamọ gbẹ. 26 Iwọ kò ti gbọ́ ri pe, lai emi li o ti ṣe e, ati pe emi li o ti dá a nigba atijọ? nisisiyi mo mu u ṣẹ, ki iwọ ki o sọ ilu-nla olodi dahoro, di okiti iparun. 27 Nitorina ni awọn olugbé wọn fi ṣe alainipa, aiya fò wọn, nwọn si dãmu: nwọn dabi koriko igbẹ, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko lori okè ilé, ati bi ọkà ti igbẹ ki o to dàgba soke. 28 Ṣugbọn mo mọ̀ ibugbe rẹ, ijadelọ rẹ, ati iwọle rẹ, ati irúnu rẹ si mi. 29 Nitori irúnu rẹ si mi, ati igberaga rẹ, ti goke wá si eti mi, nitorina ni emi o ṣe fi ìwọ mi kọ́ ọ ni imú, ati ijanu mi si ète rẹ, emi o si mu ọ pada li ọ̀na ti o ba wá. 30 Eyi ni o si jẹ àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun yi; ati li ọdun keji eyiti o sọ jade ninu ọkanna: ati li ọdun kẹta ẹ fọnrugbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba àjara, ki ẹ si jẹ eso wọn. 31 Ati iyokù ti o sala ninu ile Juda yio tun fi gbòngbo mulẹ nisalẹ, yio si so eso loke: 32 Nitori lati Jerusalemu ni iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o sala lati oke Sioni wá: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi. 33 Nitorina bayi ni Oluwa wi niti ọba Assiria, on kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio si mu asà wá siwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio wà odi tì i. 34 Li ọ̀na ti o ba wá, li ọkanna ni yio bá padà, kò si ni wá si ilu yi, li Oluwa wi. 35 Nitori emi o dãbo bò ilu yi lati gbà a nitoriti emi tikala mi, ati nitoriti Dafidi iranṣẹ mi. 36 Angeli Oluwa si jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan o le ẹgbẹ̃dọgbọn ni budo awọn ara Assiria; nigbati nwọn si dide lowurọ kùtukutu, kiyesi i, gbogbo wọn jẹ okú. 37 Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si padà, o si ngbe Ninefe. 38 O si di igbati o ṣe, bi o ti ntẹriba ni ile Nisroki oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣaresari awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a; nwọn si salà si ilẹ Armenia: Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Isaiah 38

Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀

1 LI ọjọ wọnni Hesekiah ṣaisàn de oju ikú. Woli Isaiah ọmọ Amosi si wá sọdọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Bayi ni Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́: nitori iwọ o kú, o ki yio si yè. 2 Nigbana ni Hesekiah yi oju rẹ̀ si ogiri, o si gbadura si Oluwa. 3 O si wipe, Nisisiyi, Oluwa, mo bẹ̀ ọ, ranti bi mo ti rìn niwaju rẹ li otitọ ati pẹlu aiya pipé, ati bi mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún pẹrẹ̀pẹrẹ̀. 4 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Isaiah wá, wipe, 5 Lọ, si wi fun Hesekiah pe, Bayi ni Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, mo ti gbọ́ adura rẹ, mo ti ri omije rẹ: kiyesi i emi o fi ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ. 6 Emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria: emi o si dãbò bò ilu yi. 7 Eyi yio sì jẹ àmi fun ọ lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti o ti sọ; 8 Kiyesi i, emi o tún mu ìwọn òjiji ti o ti sọkalẹ lara agogo-õrùn Ahasi pada ni ìwọn mẹwa. Bẹ̃ni õrun pada ni ìwọn mẹwa ninu ìwọn ti o ti sọkalẹ.

Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ

9 Iwe Hesekiah ọba Juda, nigbati o fi ṣaisàn, ti o si sàn ninu aisàn rẹ̀: 10 Mo ni, ni ìke-kuro ọjọ mi, emi o lọ si ẹnu-ọnà isà-okú; a dù mi ni iyokù ọdun mi. 11 Mo ni, emi kì yio ri Oluwa, ani Oluwa, ni ilẹ alãyè: emi kì yio ri enia mọ lãrin awọn ti ngbé ibi idakẹ. 12 Ọjọ ori mi lọ, a si ṣi i kuro lọdọ mi bi àgọ olùṣọ agutan: mo ti ké ẹmi mi kuro bi ahunṣọ: yio ké mi kuro bi fọ́nran-òwu tinrin: lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi. 13 Mo ṣirò titi di òwurọ, pe, bi kiniun, bẹ̃ni yio fọ́ gbogbo egungun mi; lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi. 14 Bi akọ̀ tabi alapandẹ̀dẹ, bẹ̃ni mo dún; mo kãnu bi oriri: ãrẹ̀ mu oju mi fun iwòke: Oluwa, ara nni mi: ṣe onigbọwọ mi. 15 Kili emi o wi? o ti sọ fun mi, on tikalarẹ̀ si ti ṣe e: emi o ma lọ jẹjẹ fun gbogbo ọdun mi ni kikorò ọkàn mi. 16 Oluwa, nipa nkan wọnyi li enia ima wà, ati ni gbogbo nkan wọnyi ni iye ẹmi mi: bẹ̃ni iwọ o mu mi lara dá, iwọ o si mu mi yè. 17 Kiyesi i, mo ti ni ikorò nla nipò alafia: ṣugbọn iwọ ti fẹ́ ọkàn mi lati ihò idibàjẹ wá: nitori iwọ ti gbe gbogbo ẹ̀ṣẹ mi si ẹ̀hin rẹ. 18 Nitori ibojì kò le yìn ọ, ikú kò le fiyìn fun ọ: awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò kò le ni irèti otitọ rẹ. 19 Alãyè, alãyè, on ni yio yìn ọ, bi mo ti nṣe loni yi: baba yio fi otitọ rẹ hàn fun awọn ọmọ. 20 Oluwa mura tan lati gbà mi: nitorina a o kọ orin mi lara dùrù olokùn, ni gbogbo ọjọ aiye wa ni ile Oluwa. 21 Nitori Isaiah ti wipe, Ki nwọn mu ìṣu ọ̀pọtọ́, ki a si fi ṣán õwo na, yio si sàn. 22 Hesekiah pẹlu ti wipe, Kili àmi na pe emi o goke lọ si ile Oluwa?

Isaiah 39

Ọba Babiloni kọ ìwé kí Hesekaya

1 LI akoko na ni Merodaki-baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitori o ti gbọ́ pe o ti ṣaisàn, o si ti sàn. 2 Inu Hesekiah si dùn si wọn, o si fi ile iṣura hàn wọn, fadaka, ati wura, ati nkan olõrun didùn, ati ikunra iyebiye, ati ile gbogbo ìhamọra rẹ̀, ati ohun gbogbo ti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si si nkankan ti Hesekiah kò fi hàn wọn ninu ile rẹ̀, tabi ni ijọba rẹ̀. 3 Nigbana ni wolĩ Isaiah wá sọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kini awọn ọkunrin wọnyi wi? ati lati ibo ni nwọn ti wá sọdọ rẹ? Hesekiah si wi pe, Lati ilẹ jijin ni nwọn ti wá sọdọ mi, ani lati Babiloni. 4 O si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn pe, Ohun gbogbo ti o wà ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkankan ti emi kò fi hàn wọn ninu iṣura mi. 5 Nigbana ni Isaiah wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun: 6 Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi. 7 Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ: nwọn o si jẹ́ iwẹ̀fa ni ãfin ọba Babiloni. 8 Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere ni ọ̀rọ Oluwa ti iwọ ti sọ. O si wi pẹlu pe, Alafia ati otitọ́ yio sa wà li ọjọ mi.

Isaiah 40

Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Àwọn Ọmọ Israẹli

1 Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi. 2 Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo. 3 Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa. 4 Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju: 5 A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ. 6 Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́: 7 Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia. 8 Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai. 9 Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin! 10 Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀. 11 On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun.

OLUWA Kò Ní Àfijọ

12 Tali o ti wọ̀n omi ni kòto-ọwọ́ rẹ̀, ti o si ti fi ika wọ̀n ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọ̀n awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn? 13 Tali o ti tọ́ Ẹmi Oluwa, tabi ti iṣe igbimọ̀ rẹ̀ ti o kọ́ ọ? 14 Tali o mba a gbìmọ, tali o si kọ́ ọ lẹkọ́, ti o si kọ́ ọ ni ọ̀na idajọ, ti o si kọ́ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọ̀na oye hàn a? 15 Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun. 16 Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun. 17 Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ. 18 Tali ẹnyin o ha fi Ọlọrun we? tabi awòran kini ẹnyin o fi ṣe akàwe rẹ̀? 19 Oniṣọ̀na ngbẹ́ ère, alagbẹdẹ wura si nfi wura bò o, o si ndà ẹ̀wọn fadakà. 20 Ẹniti o talakà tobẹ̃ ti kò fi ni ohun ọrẹ, yàn igi ti kì yio rà; o nwá ọlọgbọn oniṣọ̀na fun ara rẹ̀ lati gbẹ́ ère gbigbẹ́ ti a ki yio ṣi nipò. 21 Ẹnyin kò ti mọ̀? ẹnyin kò ti gbọ́? a kò ti sọ fun nyin li atètekọṣe? kò iti yé nyin lati ipilẹṣẹ aiye wá? 22 On ni ẹniti o joko lori òbíri aiye, gbogbo awọn ti ngbe ibẹ si dabi ẹlẹngà; ẹniti o ta ọrun bi ohun tita, ti o si nà wọn bi àgọ lati gbe. 23 Ẹniti o nsọ awọn ọmọ-alade di ofo; o ṣe awọn onidajọ aiye bi asan. 24 Nitõtọ, a kì yio gbìn wọn; nitõtọ, a kì yio sú wọn: nitõtọ igi wọn kì yio fi gbòngbo mulẹ: on o si fẹ́ lù wọn pẹlu, nwọn o si rọ, ãja yio si mu wọn lọ bi akekù koriko. 25 Njẹ tani ẹnyin o ha fi mi we, tabi tali emi o ba dọgbà? ni Ẹni-Mimọ wi. 26 Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù. 27 Ẽṣe ti iwọ fi nwi, Iwọ Jakobu, ti iwọ si nsọ, Iwọ Israeli pe, Ọ̀na mi pamọ kuro lọdọ Oluwa, idajọ mi si rekọja kuro lọdọ Ọlọrun mi? 28 Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ́ pe, Ọlọrun aiyeraiye, Oluwa, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣãrẹ̀, bẹ̃ni ãrẹ̀ kì imu u? kò si awari oye rẹ̀. 29 O nfi agbara fun alãrẹ̀; o si fi agbara kún awọn ti kò ni ipá. 30 Ani ãrẹ̀ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rẹ̀ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹ ṣubu patapata: 31 Ṣugbọn awọn ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ́ gùn oke bi idì; nwọn o sare, kì yio si rẹ̀ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ̀ kì yio si mu wọn.

Isaiah 41

Ọlọrun fún Israẹli ní Ìdánilójú

1 DAKẸ niwaju mi, Ẹnyin erekùṣu; si jẹ ki awọn enia tún agbara wọn ṣe: jẹ ki wọn sunmọ tosí; nigbana ni ki wọn sọ̀rọ: jẹ ki a jumọ sunmọ tosí fun idajọ. 2 Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀. 3 O lepa wọn, o si kọja li alafia; nipa ọ̀na ti kò ti fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ ri. 4 Tali o ti dá a ti o si ti ṣe e, ti o npè awọn iran lati ipilẹṣẹ̀ wá? Emi Oluwa ni; ẹni-ikini, ati pẹlu ẹni-ikẹhìn; Emi na ni. 5 Awọn erekùṣu ri i, nwọn si bẹ̀ru; aiya nfò awọn opin aiye; nwọn sunmọ tosí, nwọn si wá. 6 Olukulùku ràn aladugbo rẹ̀ lọwọ; o si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ mu ara le. 7 Bẹ̃ni gbẹnàgbẹnà ngbà alagbẹdẹ wura niyànju, ati ẹniti nfi ọmọ-owú dán a, ngbà ẹniti nlù ògún niyànju; wipe, o ṣetan fun mimọlù: o si fi iṣo kàn a mọra ki o má le ṣi. 8 Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakobu ẹniti mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọrẹ mi. 9 Ẹniti mo ti mu lati opin aiye wá, ti mo ti pè ọ lati ọdọ awọn olori enia ibẹ, ti mo si wi fun ọ pe, Iwọ ni iranṣẹ mi; mo ti yàn ọ, emi kò si ni ta ọ nù, 10 Iwọ má bẹ̀ru; nitori mo wà pẹlu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: emi o fun ọ ni okun; nitõtọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitõtọ, emi o fi ọwọ́ ọ̀tun ododo mi gbe ọ sokè. 11 Kiyesi i, gbogbo awọn ti o binu si ọ ni oju o tì, nwọn o si dãmu: nwọn o dabi asan; awọn ti o si mba ọ jà yio ṣegbe. 12 Iwọ o wá wọn, iwọ kì yio si rí wọn, ani awọn ti o ba ọ jà: awọn ti o mba ọ jagun yio dabi asan, ati bi ohun ti kò si. 13 Nitori emi Oluwa Ọlọrun rẹ yio di ọwọ́ ọ̀tun rẹ mu, emi o wi fun ọ pe, Má bẹ̀ru; emi o ràn ọ lọwọ. 14 Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu kòkoro, ati ẹnyin ọkunrin Israeli; emi o ràn ọ lọwọ, bẹ̃ni Oluwa ati Oluràpada rẹ wi, Ẹni-mimọ́ Israeli. 15 Kiyesi i, emi ti ṣe ọ bi ohun-èlo ipakà mimú titun ti o ni ehín; iwọ o tẹ̀ awọn òke-nla, iwọ o si gún wọn kunná, iwọ o si sọ awọn oke kékèké di iyàngbo. 16 Iwọ o fẹ́ wọn, ẹfũfu yio si fẹ́ wọn lọ, ãjà yio si tú wọn ká: iwọ o si yọ̀ ninu Oluwa, iwọ o si ṣogo ninu Ẹni-Mimọ Israeli. 17 Nigbati talakà ati alaini nwá omi, ti kò si si, ti ahọn wọn si gbẹ fun ongbẹ, emi Oluwa yio gbọ́ ti wọn, emi Ọlọrun Israeli ki yio kọ̀ wọn silẹ. 18 Emi o ṣi odò nibi giga, ati orisún lãrin afonifoji: emi o sọ aginjù di abàta omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi. 19 Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù. 20 Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a.

OLUWA Pe Àwọn Ọlọrun Èké níjà

21 Mú ẹjọ nyin wá, ni Oluwa wi; mú ọràn dajudaju nyin jade wá, ni ọba Jakobu wi. 22 Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa. 23 Fi ohun ti mbọ̀ lẹhìn eyi hàn, ki awa ki o le mọ̀ pe ọlọrun ni nyin: nitõtọ, ẹ ṣe rere, tabi ẹ ṣe buburu, ki ẹ̀ru le bà wa, ki a le jumọ ri i. 24 Kiyesi i, lati nkan asan ni nyin, iṣẹ nyin si jẹ asan: irira ni ẹniti o yàn nyin. 25 Emi ti gbé ẹnikan dide lati ariwa, on o si wá: lati ilà-õrun ni yio ti ké pe orukọ mi: yio si wá sori awọn ọmọ-alade bi sori àmọ, ati bi alamọ̀ ti itẹ̀ erupẹ. 26 Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin. 27 Ẹni-ikini o wi fun Sioni pe, Wò o, on na nĩ: emi o fi ẹnikan ti o mú ihinrere wá fun Jerusalemu. 28 Nitori mo wò, kò si si ẹnikan; ani ninu wọn, kò si si olugbimọ̀ kan, nigbati mo bere lọwọ wọn, kò si ẹniti o le dahùn ọ̀rọ kan. 29 Kiyesi i, asan ni gbogbo wọn; asan ni iṣẹ wọn; ẹfũfu ati rudurudu ni ere didà wọn.

Isaiah 42

Iranṣẹ Ọlọrun

1 WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi. 2 On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. 3 Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ. 4 Ãrẹ̀ kì yio mú u, a kì yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye, awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ̀. 5 Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀: 6 Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi. 7 Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu. 8 Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́. 9 Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn.

Orin Ìyìn fún OLUWA

10 Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn. 11 Jẹ ki aginjù ati ilu-nla ibẹ gbé ohùn wọn soke, iletò wọnni ti Kedari ngbé: jẹ ki awọn ti ngbé apáta kọrin, jẹ ki wọn hó lati ori oke-nla wá. 12 Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu. 13 Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀.

Ọlọrun ṣe Ìlérí láti Ran Àwọn Eniyan Rẹ̀ lọ́wọ́

14 Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna. 15 Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ. 16 Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ. 17 A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.

Israẹli Kùnà láti Kẹ́kọ̀ọ́

18 Gbọ́, ẹnyin aditi; ki ẹ si wò, ẹnyin afọju ki ẹnyin ki o le ri i. 19 Tani afọju, bikoṣe iranṣẹ mi? tabi aditi, bi ikọ̀ mi ti mo rán? tani afọju bi ẹni pipé? ti o si fọju bi iranṣẹ Oluwa? 20 Ni riri nkan pupọ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi i; ni ṣiṣi eti, ṣugbọn on ko gbọ́. 21 Inu Oluwa dùn gidigidi nitori ododo rẹ̀; yio gbe ofin ga, yio si sọ ọ di ọlọlá. 22 Ṣugbọn enia ti a jà lole ti a si ko li ẹrù ni eyi: gbogbo wọn li a dẹkùn mu ninu ihò, a fi wọn pamọ ninu tubu: a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si gbà wọn; a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si wipe, Mu u pada. 23 Tani ninu nyin ti o fi eti si eyi? ti o dẹti silẹ, ti yio si gbọ́ eyi ti mbọ̀ lẹhin? 24 Tani fi Jakobu fun ikogun, ti o si fi Israeli fun ole? Oluwa ha kọ́ ẹniti a ti dẹṣẹ si? nitori nwọn kò fẹ rìn li ọ̀na rẹ̀, bẹ̃ni nwọn ko gbọ́ ti ofin rẹ̀. 25 Nitorina ni o ṣe dà irúnu ibinu rẹ̀ si i lori, ati agbara ogun: o si ti tẹ̀ iná bọ̀ ọ yika, ṣugbọn on kò mọ̀; o si jo o, ṣugbọn on kò kà a si.

Isaiah 43

OLUWA Ṣe Ìlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ. 2 Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ. 3 Nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli, Olugbala rẹ: mo fi Egipti ṣe irapada rẹ, mo si fi Etiopia ati Seba fun ọ. 4 Niwọn bi iwọ ti ṣe iyebiye to loju mi, ti iwọ ṣe ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpò rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ. 5 Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá. 6 Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkunrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá. 7 Olukuluku ẹniti a npè li orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ogo mi, mo ti mọ ọ, ani, mo ti ṣe e pé.

Ẹlẹ́rìí OLUWA ni Israẹli

8 Mu awọn afọju enia ti o li oju jade wá, ati awọn aditi ti o li eti. 9 Jẹ ki gbogbo awọn orilẹ-ède ṣa ara wọn jọ pọ̀, ki awọn enia pejọ; tani ninu wọn ti o le sọ eyi, ti o si le fi ohun atijọ han ni? jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wọn jade, ki a le dá wọn lare; nwọn o si gbọ́, nwọn o si wipe, Õtọ ni. 10 Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni Oluwa wi, ati iranṣẹ mi ti mo ti yàn: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki ẹ si gbà mi gbọ́ ki o si ye nyin pe, Emi ni; a kò mọ̀ Ọlọrun kan ṣãju mi, bẹ̃ni ọkan kì yio si hù lẹhin mi. 11 Emi, ani emi ni Oluwa; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan. 12 Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati ko si ajeji ọlọrun kan lãrin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi, li Oluwa wi, pe, Emi li Ọlọrun. 13 Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?

Sísá kúrò ní Babiloni

14 Bayi li Oluwa, olurapada nyin, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ̀ igbe-ayọ̀ wọn. 15 Emi ni Oluwa, Ẹni-Mimọ́ nyin, ẹlẹda Israeli Ọba nyin. 16 Bayi li Oluwa wi, ẹniti o la ọ̀na ninu okun, ati ipa-ọ̀na ninu alagbara omi; 17 Ẹniti o mu kẹkẹ ati ẹṣin jade, ogun ati agbara; nwọn o jumọ dubulẹ, nwọn kì yio dide: nwọn run, a pa wọn bi owú fitila. 18 Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn. 19 Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ̀ ọ bi? lõtọ, emi o là ọ̀na kan ninu aginju, ati odò li aṣalẹ̀. 20 Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi; 21 Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn.

Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli

22 Ṣugbọn iwọ kò ké pe mi, Jakobu; ṣugbọn ãrẹ̀ mu ọ nitori mi, iwọ Israeli. 23 Iwọ ko mu ọmọ-ẹran ẹbọ sisun rẹ fun mi wá; bẹ̃ni iwọ ko fi ẹbọ rẹ bu ọlá fun mi. Emi ko fi ọrẹ mu ọ sìn, emi ko si fi turari da ọ li agara. 24 Iwọ ko fi owo rà kalamu olõrun didun fun mi, bẹ̃ni iwọ ko fi ọra ẹbọ rẹ yó mi; ṣugbọn iwọ fi ẹ̀ṣẹ rẹ mu mi ṣe lãla, iwọ si fi aiṣedẽde rẹ da mi li agara. 25 Emi, ani emi li ẹniti o pa irekọja rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalami, emi ki yio si ranti ẹ̀ṣẹ rẹ. 26 Rán mi leti: ki a jumọ sọ ọ; iwọ rò, ki a le da ọ lare. 27 Baba rẹ iṣãju ti ṣẹ̀, awọn olukọni rẹ ti yapa kuro lọdọ mi. 28 Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ́ na di aimọ́, mo si ti fi Jakobu fun egún, ati Israeli fun ẹ̀gan.

Isaiah 44

Ọlọrun kanṣoṣo ni OLUWA

1 ṢUGBỌN nisisiyi, gbọ́, iwọ Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ẹniti mo ti yàn: 2 Bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, ti o mọ ọ lati inu wá, ti yio si ràn ọ lọwọ; Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, iranṣẹ mi; ati iwọ Jeṣuruni ti mo ti yàn. 3 Nitori emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣàn-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ. 4 Nwọn o si hù soke lãrin koriko, bi igi willo leti ipadò. 5 Ọkan yio wipe, ti Oluwa li emi, omiran yio si pe ara rẹ̀ nipa orukọ Jakobu; omiran yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọ pe, on ni ti Oluwa, yio si pe apele rẹ̀ nipa orukọ Israeli. 6 Bayi ni Oluwa wi, Ọba Israeli, ati Olurapada rẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun; Emi ni ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin; ati lẹhin mi ko si Ọlọrun kan. 7 Tani yio si pè bi emi, ti yio si sọ ọ ti yio si tò o lẹsẹ-ẹsẹ fun mi, lati igbati mo ti yàn awọn enia igbani? ati nkan wọnni ti mbọ̀, ti yio si ṣẹ, ki nwọn fi hàn fun wọn. 8 Ẹ má bẹ̀ru, ẹ má si foyà; emi ko ha ti mu nyin gbọ́ lati igba na wá, nkò ha si ti sọ ọ? ẹnyin na ni ẹlẹri mi. Ọlọrun kan mbẹ lẹhin mi bi? kò si Apata kan, emi ko mọ̀ ọkan.

A fi Ìwà Ìbọ̀rìṣà ṣẹ̀sín

9 Asan ni gbogbo awọn ti ngbẹ ere; nkan iyebiye wọn ki yio si lerè; awọn tikala wọn li ẹlẹri ara wọn: nwọn kò riran, bẹ̃ni nwọn kò mọ̀; ki oju ba le tì wọn. 10 Tani yio gbẹ́ oriṣa, tabi ti yio dà ere ti kò ni ère kan? 11 Kiyesi i, oju o tì gbogbo awọn ẹgbẹ́ rẹ̀; awọn oniṣọna, enia ni nwọn: jẹ ki gbogbo wọn kò ara wọn jọ, ki nwọn dide duro; nwọn o bẹ̀ru, oju o si jumọ tì wọn. 12 Alagbẹdẹ rọ ãke kan, o ṣiṣẹ ninu ẹyín, o fi ọmọ-owú rọ ọ, o si fi agbara apá rẹ̀ ṣe e: ebi npa a pẹlu, agbara rẹ̀ si tan; ko mu omi, o si rẹ̀ ẹ. 13 Gbẹnàgbẹnà ta okùn rẹ̀, o si fi nkan pupa sàmi rẹ̀, o fi ìfá fá a, o si fi kọmpassi là a birikiti: o sì yá a li aworán ọkunrin, gẹgẹ bi ẹwà enia, ki o le ma gbe inu ile. 14 O bẹ́ igi kedari lu ilẹ fun ra rẹ̀, o si mu igi kipressi ati oaku, o si mu u le fun ra rẹ̀ ninu awọn igi igbó: o gbìn igi aṣi, ojò si mu u dagba. 15 Nigbana ni yio jẹ ohun idana fun enia: nitori yio mu ninu wọn, yio si fi yá iná; lõtọ, o dá iná, o si din akara, lõtọ, o ṣe ọlọrun fun ra rẹ̀, o si nsìn i; o gbẹ ẹ li ere, o si nforibalẹ fun u. 16 Apakan ninu rẹ̀ li o fi dá iná, apakan ninu rẹ̀ li o fi jẹ ẹran: o sun sisun, o si yo, o yá iná pẹlu, o si wipe, Ahã, ara mi gbona, mo ti ri iná. 17 Iyokù rẹ̀ li o si fi ṣe ọlọrun, ani ere gbigbẹ́ rẹ̀, o foribalẹ fun u, o sìn i, o gbadura si i, o si wipe, Gbà mi; nitori iwọ li ọlọrun mi. 18 Nwọn kò mọ̀, oye ko si ye wọn: nitori o dí wọn li oju, ki nwọn ki o má le ri; ati aiya wọn, ki oye ki o má le ye wọn. 19 Kò si ẹniti o rò li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni ko si imọ̀ tabi oye lati wipe, Mo ti fi apakan rẹ̀ da iná; mo si din akara pẹlu lori ẹyin iná rẹ̀: mo ti sun ẹran, mo si jẹ ẹ: emi o ha fi iyokù rẹ̀ ṣe irira? emi o ha foribalẹ fun ìti igi? 20 O fi ẽru bọ́ ara rẹ̀: aiya ẹtàn ti dari rẹ̀ si apakan, ti kò le gbà ọkàn rẹ̀ là, bẹ̃ni kò le wipe, Eke ko ha wà li ọwọ́ ọtun mi?

OLUWA, Ẹlẹ́dàá ati Olùgbàlà

21 Ranti wọnyi, Jakobu ati Israeli; nitori iwọ ni iranṣẹ mi: Emi ti mọ ọ; iranṣẹ mi ni iwọ, Israeli; iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi. 22 Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada. 23 Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli. 24 Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye. 25 Ẹniti o sọ àmi awọn eke di asan, ti o si bà awọn alafọṣẹ li ori jẹ, ti o dá awọn ọlọgbọn pada, ti o si sọ imọ̀ wọn di wère. 26 Ti o fi ìdi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ̀ mulẹ, ti o si mu ìmọ awọn ikọ̀ rẹ̀ ṣẹ; ti o wi fun Jerusalemu pe, A o tẹ̀ ọ dó; ati fun gbogbo ilu Juda pe, A o kọ́ nyin, emi o si gbe gbogbo ahoro rẹ̀ dide: 27 Ti o wi fun ibú pe, Gbẹ, emi o si mu gbogbo odò rẹ gbẹ. 28 Ti o wi niti Kirusi pe, Oluṣọ-agutan mi ni, yío si mu gbogbo ifẹ mi ṣẹ: ti o wi niti Jerusalemu pe, A o kọ́ ọ: ati niti tempili pe, A o fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ.

Isaiah 45

OLUWA Yan Kirusi

1 BAYI ni Oluwa wi fun ẹni-ororo rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ́ ọtún rẹ̀ mu, lati ṣẹ́gun awọn orilẹ-ède niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹgbẹ awọn ọba, lati ṣi ilẹkùn mejeji niwaju rẹ̀, a ki yio si tì ẹnu-bode na; 2 Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji. 3 Emi o si fi iṣura okùnkun fun ọ, ati ọrọ̀ ti a pamọ nibi ikọkọ, ki iwọ le mọ̀ pe, emi Oluwa, ti o pè ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli. 4 Nitori Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ayanfẹ mi, emi ti pè ọ li orukọ rẹ: mo ti fi apele kan fun ọ, bi iwọ ko tilẹ ti mọ̀ mi. 5 Emi li Oluwa, ko si ẹlomiran, kò si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li àmure, bi iwọ kò tilẹ ti mọ̀ mi. 6 Ki nwọn le mọ̀ lati ila-õrun, ati lati iwọ-õrun wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi; Emi ni Oluwa, ko si ẹlomiran. 7 Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi. 8 Kán silẹ, ẹnyin ọrun, lati oke wá, ki ẹ si jẹ ki ofurufu rọ̀ ododo silẹ; jẹ ki ilẹ ki o là, ki o si mu igbala jade; si jẹ ki ododo ki o hù soke pẹlu rẹ̀; Emi Oluwa li o dá a.

OLUWA Ẹlẹ́dàá Ayé ati Ìtàn

9 Egbe ni fun ẹniti o mbá Elẹda rẹ̀ jà, apãdi ninu awọn apãdi ilẹ! Amọ̀ yio ha wi fun ẹniti o mọ ọ pe, Kini iwọ nṣe? tabi iṣẹ rẹ pe, On kò li ọwọ́? 10 Egbe ni fun ẹniti o wi fun baba rẹ̀ pe, Kini iwọ bi? tabi fun obinrin nì pe, Kini iwọ bi? 11 Bayi li Oluwa wi, Ẹni-Mimọ Israeli, ati Ẹlẹda rẹ̀, Bere nkan ti mbọ̀ lọwọ mi, niti awọn ọmọ mi ọkunrin, ati niti iṣẹ ọwọ mi, ẹ paṣẹ fun mi. 12 Mo ti dá aiye, mo si ti da enia sori rẹ̀; Emi, ani ọwọ́ mi, li o ti nà awọn ọrun, gbogbo awọn ogun wọn ni mo si ti paṣẹ fun. 13 Mo ti gbe e dide ninu ododo, emi o si mu gbogbo ọ̀na rẹ̀ tọ́; on o kọ́ ilu mi, yio si dá awọn ondè mi silẹ: ki iṣe fun iye owo tabi ère, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 14 Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran. 15 Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala. 16 Oju yio tì wọn, gbogbo wọn o si dãmu pọ̀; gbogbo awọn ti nṣe ere yio si jumọ lọ si idãmu. 17 Ṣugbọn a o fi igbala ainipẹkun gba Israeli là ninu Oluwa: oju ki yio tì nyin, bẹ̃ni ẹ ki yio dãmu titi aiye ainipẹkun. 18 Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran. 19 Emi kò sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kò wi fun iru-ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi Oluwa li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ́ hàn.

OLUWA Gbogbo Ayé ati Àwọn Oriṣa Babiloni

20 Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni. 21 Ẹ sọ ọ, ki ẹ si mu wá, lõtọ, ki nwọn ki o jọ gbimọ̀ pọ̀: tali o mu ni gbọ́ eyi lati igbãni wa? tali o ti sọ ọ lati igba na wá? emi Oluwa kọ? ko si Ọlọrun miran pẹlu mi; Ọlọrun ododo ati Olugbala; ko si ẹlomiran lẹhin mi. 22 Kọju si mi, ki a si gba nyin là, gbogbo opin aiye: nitori emi li Ọlọrun, ko si ẹlomiran. 23 Mo ti fi ara mi bura, ọ̀rọ na ti ti ẹnu ododo mi jade, ki yio si pada, pe, Gbogbo ẽkún yio kunlẹ fun mi, gbogbọ ahọn yio bura. 24 Lõtọ, a o wipe, ninu Oluwa li emi ni ododo ati agbara: sọdọ rẹ̀ ni gbogbo enia yio wá; oju o si tì gbogbo awọn ti o binu si i. 25 Ninu Oluwa li a o dá gbogbo iru-ọmọ Israeli lare, nwọn o si ṣogo.

Isaiah 46

1 BELI tẹriba, Nebo bẹrẹ̀, oriṣa wọn wà lẹhin awọn ẹranko, ati lẹhin ohun-ọ̀sin; a di ẹrù wiwo rù nyin; ẹrù fun awọn ẹranko ti ãrẹ̀ mu. 2 Nwọn bẹ̀rẹ, nwọn jumọ tẹriba; nwọn kò le gbà ẹrù na silẹ, ṣugbọn awọn tikala wọn lọ si igbèkun. 3 Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá. 4 Ani titi de ogbó emi na ni; ani titi de ewú li emi o rù nyin; emi ti ṣe e, emi o si gbe, nitõtọ emi o rù, emi o si gbàla. 5 Tani ẹnyin o fi mi we, ti yio si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gba? 6 Nwọn da wura lati inu apò wá, nwọn si fi iwọ̀n wọ̀n fadaka, nwọn bẹ̀ alagbẹdẹ wura, o si fi i ṣe oriṣa: nwọn tẹriba, nwọn si nsìn. 7 Nwọn gbe e le ejika, nwọn rù u, nwọn si fi i sipò rẹ̀; o si duro: ki yio kuro ni ipò rẹ̀; nitõtọ, ẹnikan yio kọ si i, ṣugbọn ki yio dahùn: bẹ̃ni ki yio gbà a kuro ninu wahala rẹ̀. 8 Ẹ ranti eyi, ẹ si fi ara nyin hàn bi ọkunrin: ẹ gbà a si ọkàn, ẹnyin alarekọja. 9 Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi. 10 Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi. 11 Ẹniti npe idì lati ilà-õrun wá: ọkunrin na ti o mu ìmọ mi ṣẹ lati ilẹ jijìn wá: lõtọ, emi ti sọ ọ, emi o si mu u ṣẹ; emi ti pinnu rẹ̀, emi o si ṣe e pẹlu. 12 Gbọ́ ti emi, ẹnyin alagidi ọkàn, ti o jinà si ododo: 13 Emi mu ododo mi sunmọ tosí; ki yio si jina rére, igbala mi ki yio si duro pẹ́: emi o si fi igbala si Sioni fun Israeli ogo mi.

Isaiah 47

Ìdájọ́ lórí Babiloni

1 SỌKALẸ, si joko ninu ekuru, iwọ wundia ọmọbinrin Babiloni, joko ni ilẹ: itẹ́ kò si, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea: nitori a kì o pè ọ ni ẹlẹ́gẹ on aláfẹ mọ. 2 Gbe ọlọ, si lọ̀ iyẹfun, ṣi iboju rẹ, ká aṣọ ẹsẹ, ká aṣọ itan, là odo wọnni kọja. 3 A o ṣi ihoho rẹ, a o si ri itiju rẹ pẹlu; emi o gbẹsan, enia kì yio sí lati da mi duro. 4 Olurapada wa, Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀, Ẹni-Mimọ Israeli. 5 Joko, dakẹ jẹ, lọ sinu okùnkun, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea, nitori a ki yio pe ọ ni Iyálode awọn ijọba mọ. 6 Emi ti binu si enia mi, emi ti sọ ilẹ ini mi di aimọ́, mo si ti fi wọn le ọ lọwọ: iwọ kò kãnu wọn, iwọ fi ajàga wuwo le awọn alagba lori. 7 Iwọ si wipe, Emi o ma jẹ Iyalode titi lai: bẹ̃ni iwọ kò fi nkan wọnyi si aiya rẹ, bẹ̃ni iwọ kò ranti igbẹhin rẹ. 8 Nitorina gbọ́ eyi, iwọ alafẹ́, ti o joko li ainani, ti o wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, kò si si ẹlomiran lẹhin mi: emi ki yio joko bi opo, bẹ̃ni emi ki yio mọ̀ òfo ọmọ. 9 Ṣugbọn nkan meji wọnyi ni yio deba ọ li ojiji, li ọjọ kan, òfo ọmọ ati opo: nwọn o ba ọ perepere, nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ ajẹ́ rẹ, ati nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ afọṣẹ rẹ. 10 Nitori ti iwọ ti gbẹkẹle ìwa buburu rẹ: iwọ ti wipe, Kò si ẹnikan ti o ri mi. Ọgbọ́n rẹ ati ìmọ rẹ, o ti mu ọ ṣinà; iwọ si ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, ko si ẹlomiran lẹhin mi. 11 Nitorina ni ibi yio ṣe ba ọ; iwọ ki yio mọ̀ ibẹrẹ rẹ̀: ibi yio si ṣubu lù ọ; ti iwọ kì yio le mu kuro: idahoro yio deba ọ lojiji, iwọ kì yio si mọ̀. 12 Duro nisisiyi, ti iwọ ti iṣẹ afọṣẹ rẹ, ati ọpọlọpọ iṣẹ ajẹ́ rẹ, eyi ti o ti fi nṣe iṣẹ iṣe lati igba ewe rẹ wá; bi o ba ṣepe o lè jẹ erè fun ọ, bi o ba ṣe pe iwọ lè bori. 13 Arẹ̀ mu ọ nipa ọpọlọpọ ìgbimọ rẹ. Jẹ ki awọn awoye-ọrun, awọn awoye-irawọ, awọn afi-oṣupasọ-asọtẹlẹ, dide duro nisisiyi, ki nwọn si gbà ọ lọwọ nkan wọnyi ti yio ba ọ. 14 Kiye si i, nwọn o dabi akekù koriko: iná yio jo wọn: nwọn ki yio gba ara wọn lọwọ agbara ọwọ́ iná; ẹyin iná kan ki yio si lati yá, tabi iná lati joko niwaju rẹ̀. 15 Bayi ni awọn ti iwọ ti ba ṣiṣẹ yio jẹ fun ọ, awọn oniṣowo rẹ, lati ewe rẹ wá; nwọn o kiri lọ, olukuluku si ẹkùn rẹ̀; ko si ẹnikan ti yio gbà ọ.

Isaiah 48

Ọlọrun ni OLUWA Ọjọ́ Iwájú

1 GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo. 2 Nitori nwọn npè ara wọn ni ti ilu mimọ́ nì, nwọn si gbé ara wọn le Ọlọrun Israeli: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. 3 Emi ti sọ nkan ti iṣãju wọnni lati ipilẹṣẹ; nwọn si ti jade lati ẹnu mi lọ, emi si fi wọn hàn; emi ṣe wọn lojijì, nwọn si ti ṣẹ. 4 Nitori emi mọ̀ pe olori-lile ni iwọ, ọrùn rẹ jẹ iṣan irin, iwaju rẹ si jẹ idẹ. 5 Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ. 6 Iwọ ti gbọ́, wò gbogbo eyi; ẹnyin kì yio ha sọ ọ? Emi ti fi ohun titun hàn ọ lati igba yi lọ, ani nkan ti o pamọ́, iwọ kò si mọ̀ wọn. 7 Nisisiyi li a dá wọn, ki isi ṣe li atetekọṣe; ani ṣaju ọjọ na ti iwọ kò gbọ́ wọn; ki iwọ má ba wipe, Kiyesi i, emi mọ̀ wọn. 8 Lõtọ, iwọ kò gbọ́; lõtọ, iwọ kò mọ̀; lõtọ lati igba na eti rẹ̀ kò ṣi: nitori ti emi mọ̀ pe, iwọ o hùwa arekerekè, gidigidi li a si pè ọ li olurekọja lati inu wá. 9 Nitori orukọ mi emi o mu ibinu mi pẹ, ati nitori iyìn mi, emi o fàsẹhin nitori rẹ, ki emi má ba ké ọ kuro. 10 Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala. 11 Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran.

Kirusi Alákòóso tí OLUWA Yàn

12 Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin. 13 Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro. 14 Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea. 15 Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde. 16 Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ́ eyi; lati ipilẹ̀ṣẹ emi kò sọ̀rọ ni ikọ̀kọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, on Ẹmi rẹ̀, li o ti rán mi.

Ìlànà Ọlọrun fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

17 Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ. 18 Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun. 19 Iru-ọmọ rẹ pẹlu iba dabi iyanrìn, ati ọmọ-bibi inu rẹ bi tãra rẹ̀; a ki ba ti ke orukọ rẹ̀ kuro, bẹ̃ni a kì ba pa a run kuro niwaju mi. 20 Ẹ jade kuro ni Babiloni, ẹ sá kuro lọdọ awọn ara Kaldea, ẹ fi ohùn orin sọ ọ, wi eyi, sọ ọ jade titi de opin aiye; ẹ wipe, Oluwa ti rà Jakobu iranṣẹ rẹ̀ pada. 21 Ongbẹ kò si gbẹ wọn, nigbati o mu wọn là aginjù wọnni ja; o mu omi ṣàn jade lati inu apata fun wọn, o sán apáta pẹlu, omi si tú jade. 22 Alafia kò si fun awọn enia buburu, li Oluwa wi.

Isaiah 49

Israẹli, Ìmọ́lẹ̀ fún Ayé

1 Ẹ gbọ ti emi, ẹnyin erekùṣu; ki ẹ si fi etí silẹ, ẹnyin enia lati ọ̀na jijìn wá; Oluwa ti pè mi lati inu wá; lati inu iya mi li o ti dá orukọ mi. 2 O si ti ṣe ẹnu mi bi idà mimú; ninu ojìji ọwọ́ rẹ̀ li o ti pa mi mọ, o si sọ mi di ọfà didán; ninu apó rẹ̀ li o ti pa mi mọ́; 3 O si wi fun mi pe, Iwọ ni iranṣẹ mi, Israeli, ninu ẹniti a o yìn mi logo. 4 Nigbana ni mo wi pe, Emi ti ṣiṣẹ́ lasan, emi ti lò agbara mi lofo, ati lasan: nitõtọ idajọ mi mbẹ lọdọ Oluwa, ati iṣẹ mi lọdọ Ọlọrun mi. 5 Ati nisisiyi, li Oluwa wi, ẹni ti o mọ mi lati inu wá lati ṣe iranṣẹ rẹ̀, lati mu Jakobu pada wá sọdọ rẹ̀, lati ṣà Israeli jọ, ki emi le ni ogo loju Oluwa, Ọlọrun mi yio si jẹ́ agbara mi. 6 O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye. 7 Bayi ni Oluwa, Olurapada Israeli, ati Ẹni-Mimọ rẹ wi, fun ẹniti enia ngàn, fun ẹniti orilẹ-ède korira, fun iranṣẹ awọn olori, pe, Awọn ọba yio ri, nwọn o si dide, awọn ọmọ-alade pẹlu yio wolẹ sìn, nitori Oluwa ti iṣe olõtọ, Ẹni-Mimọ Israeli, on li o yàn ọ.

Ìmúpadàbọ̀sípò Jerusalẹmu

8 Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni. 9 Ki iwọ ki o le wi fun awọn igbekùn pe, Ẹ jade lọ; fun awọn ti o wà ni okùnkun pe, Ẹ fi ara nyin hàn. Nwọn o jẹ̀ li ọ̀na wọnni, pápa ijẹ wọn o si wà ni gbogbo ibi giga. 10 Ebi kì yio pa wọn, bẹ̃ni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; õru kì yio mu wọn, bẹ̃ni õrùn kì yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣãnu fun wọn yio tọ́ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn. 11 Emi o si sọ gbogbo awọn òke-nla mi wọnni di ọ̀na, a o si gbe ọ̀na opopo mi wọnni ga. 12 Kiye si i, awọn wọnyi yio wá lati ọ̀na jijìn: si wò o, awọn wọnyi lati ariwa wá; ati lati iwọ-õrun wá, ati awọn wọnyi lati ilẹ Sinimu wá. 13 Kọrin, ẹnyin ọrun; ki o si yọ̀, iwọ aiye; bú jade ninu orin, ẹnyin oke-nla: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, yio si ṣãnu fun awọn olupọnju rẹ̀. 14 Ṣugbọn Sioni wipe, Oluwa ti kọ̀ mi silẹ; Oluwa mi si ti gbagbe mi. 15 Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ. 16 Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo. 17 Awọn ọmọ rẹ yára; awọn oluparun rẹ ati awọn ti o fi ọ ṣofò yio ti ọdọ rẹ jade. 18 Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo. 19 Nitori ibi ofò rẹ, ati ibi ahoro rẹ wọnni, ati ilẹ iparun rẹ, yio tilẹ há jù nisisiyi, nitori awọn ti ngbe inu wọn, awọn ti o gbe ọ mì yio si jinà rére. 20 Awọn ọmọ-ọmọ rẹ ti o ti nù yio tun wi li eti rẹ pe, Ayè kò gbà mi, fi ayè fun mi lati ma gbé. 21 Nigbana ni iwọ o wi li ọkàn rẹ pe, Tali o bi awọn wọnyi fun mi, mo sa ti wà li ailọmọ ati li àgan, igbèkun ati ẹni-iṣikiri? tani o si ti tọ́ awọn wọnyi dagba? Kiyesi i, a fi emi nikan silẹ, awọn wọnyi, nibo ni nwọn gbe ti wà. 22 Bayi ni Oluwa Jehofa wi, Kiyesi i, emi o gbe ọwọ́ mi soke si awọn Keferi, emi o si gbe ọpágun mi soke si awọn enia, nwọn o si gbe awọn ọmọkunrin rẹ wá li apa wọn, a o si gbe awọn ọmọbinrin rẹ li ejìka wọn. 23 Awọn ọba yio jẹ baba olutọju rẹ, awọn ayaba wọn yio si jẹ iya olutọju rẹ; ni idojubolẹ ni nwọn o ma tẹriba fun ọ, nwọn o si lá ekuru ẹsẹ rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa; nitori oju kì yio tì awọn ti o ba duro dè mi. 24 A ha le gba ikogun lọwọ alagbara bi? tabi a le gbà awọn ondè lọwọ awọn ẹniti nwọn tọ́ fun? 25 Ṣugbọn bayi ni Oluwa wi, a o tilẹ̀ gbà awọn ondè kuro lọwọ awọn alagbara, a o si gbà ikogun lọwọ awọn ẹni-ẹ̀ru; nitori ẹniti o mba ọ jà li emi o ba jà, emi o si gbà awọn ọmọ rẹ là. 26 Awọn ti o ni ọ lara li emi o fi ẹran ara wọn bọ́, nwọn o mu ẹjẹ ara wọn li amuyo bi ọti-waini didùn: gbogbo ẹran-ara yio si mọ̀ pe, Emi Oluwa ni Olugbala ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara ti Jakobu.

Isaiah 50

1 BAYI ni Oluwa wi, Nibo ni iwe ikọsilẹ iyá nyin gbe wà, ẹniti mo ti kọ̀ silẹ? tabi tani ninu awọn onigbese mi ti mo ti tà nyin fun? Kiyesi i, nitori aiṣedẽde nyin li ẹnyin ti tà ara nyin, ati nitori irekọja nyin li a ṣe kọ̀ iyá nyin silẹ. 2 Nitori nigbati mo de, kò si ẹnikan? nigbati mo pè, kò si ẹnikan lati dahùn? Ọwọ́ mi ha kuru tobẹ̃ ti kò fi le rapada? tabi emi kò ha li agbara lati gbani? Kiyesi i, ni ibawi mi mo gbẹ okun, mo sọ odò nla di aginjù, ẹja wọn nrùn nitori ti omi kò si, nwọn si kú fun ongbẹ. 3 Mo fi ohun dúdu wọ̀ awọn ọrun, mo si fi aṣọ ọfọ̀ ṣe ibora wọn.

Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA

4 Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ. 5 Oluwa Jehofa ti ṣí mi li eti, emi kò si ṣe aigbọràn, bẹ̃ni emi kò yipada. 6 Mo fi ẹ̀hìn mi fun awọn aluni, ati ẹ̀rẹkẹ mi fun awọn ti ntú irun: emi kò pa oju mi mọ́ kuro ninu itìju ati itutọ́ si. 7 Nitori Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ: nitorina emi kì yio dãmu; nitorina ni mo ṣe gbe oju mi ró bi okuta lile, emi si mọ̀ pe oju kì yio tì mi. 8 Ẹniti o dá mi lare wà ni tosí, tani o ba mi jà? jẹ ki a duro pọ̀: tani iṣe ẹlẹ́jọ mi? jẹ ki o sunmọ mi. 9 Kiye si i, Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ, tani o dá mi li ẹbi? wò o, gbogbo wọn o di ogbó bi ẹwù; kokòro yio jẹ wọn run. 10 Tani ninu nyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ti o gba ohùn iranṣẹ rẹ̀ gbọ́, ti nrìn ninu okùnkun, ti kò si ni imọlẹ? jẹ ki on gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa, ki o si fi ẹ̀hìn tì Ọlọrun rẹ̀. 11 Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.

Isaiah 51

Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Jerusalẹmu

1 GBỌ ti emi, ẹnyin ti ntẹle ododo, ẹnyin ti nwá Oluwa; wò apáta nì ninu eyiti a ti gbẹ́ nyin, ati ihò kòto nì nibiti a gbe ti wà nyin. 2 Ẹ wò Abrahamu baba nyin, ati Sara ti o bi nyin; nitori on nikan ni mo pè, mo si sure fun u, mo si mu u pọ̀ si i. 3 Nitori Oluwa yio tù Sioni ninu; yio tú gbogbo ibi ofo rẹ̀ ninu; yio si ṣe aginju rẹ̀ bi Edeni, ati aṣálẹ rẹ̀ bi ọgbà Oluwa, ayọ̀ ati inudidùn li a o ri ninu rẹ̀, idupẹ, ati ohùn orin. 4 Tẹtilelẹ si mi, ẹnyin enia mi; si fi eti si mi, iwọ orilẹ-ède mi: nitori ofin kan yio ti ọdọ mi jade lọ, emi o si gbe idajọ mi kalẹ fun imọlẹ awọn enia. 5 Ododo mi wà nitosí; igbala mi ti jade lọ, apá mi yio si ṣe idajọ awọn enia; awọn erekùṣu yio duro dè mi, apá mi ni nwọn o si gbẹkẹle. 6 Ẹ gbé ojú nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ́ lọ bi ẹ̃fin, aiye o si di ogbó bi ẹwù, awọn ti ngbe inu rẹ̀ yio si kú bakanna: ṣugbọn igbala mi o wà titi lai, ododo mi kì yio si parẹ́. 7 Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn. 8 Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran. 9 Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́? 10 Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja? 11 Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ. 12 Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko. 13 Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà? 14 Ondè ti a ti ṣí nipo yara ki a ba le tú u silẹ, ati ki o má ba kú sinu ihò, tabi ki onjẹ rẹ̀ má ba tán. 15 Ṣugbọn emi Oluwa Ọlọrun rẹ ti o pin okun ni iyà, eyi ti ìgbi rẹ̀ nhó; Oluwa awọn ọmọ-ogun ni orukọ rẹ̀. 16 Emi si ti fi ọ̀rọ mi si ẹnu rẹ, mo si ti bò ọ mọlẹ ni ojiji ọwọ́ mi, ki emi ki o le gbìn awọn ọrun, ki emi si le fi ipilẹ aiye sọlẹ, ati ki emi le wi fun Sioni pe, Iwọ ni enia mi.

Òpin Ìjìyà Jerusalẹmu

17 Ji, ji, dide duro, iwọ Jerusalemu, ti o ti mu li ọwọ́ Oluwa ago irúnu rẹ̀; iwọ ti mu gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago ìwarìri, iwọ si fọ́n wọn jade. 18 Kò si ẹnikan ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti o bí lati tọ́ ọ; bẹ̃ni kò si ẹniti o fà a lọwọ, ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti on tọ́ dàgba. 19 Ohun meji wọnyi li o débá ọ: tani o kãnu fun ọ? idahoro, on iparun, ati ìyan, on idà: nipa tani emi o tù ọ ninu? 20 Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ. 21 Nitorina gbọ́ eyi na, iwọ ẹniti a pọ́n loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn kì iṣe nipa ọti-waini: 22 Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ. 23 Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.

Isaiah 52

Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu

1 JI! ji! gbe agbara rẹ wọ̀, iwọ Sioni; gbe aṣọ ogo rẹ wọ̀, iwọ Jerusalemu, ilu mimọ́: nitori lati igbayi lọ, alaikọla on alaimọ́ kì yio wọ̀ inu rẹ mọ. 2 Gbọ̀n ekuru kuro li ara rẹ, dide, joko, iwọ Jerusalemu: tú ọjá kuro li ọrùn rẹ, iwọ ondè ọmọbinrin Sioni. 3 Nitori bayi li Oluwa wi, a ti tà nyin lọfẹ, a o si rà nyin pada laisanwo. 4 Nitori bayi li Oluwa Jehofa wi, Awọn enia mi sọkalẹ lọ si Egipti li atijọ lati ṣe atipo nibẹ; ara Assiria si ni wọn lara lainidi. 5 Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi. 6 Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni. 7 Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba! 8 Awọn alóre rẹ yio gbe ohùn soke; nwọn o jumọ fi ohùn kọrin: nitori nwọn o ri li ojukoju, nigbati Oluwa ba mu Sioni pada. 9 Bú si ayọ̀, ẹ jumọ kọrin, ẹnyin ibi ahoro Jerusalemu: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, o ti rà Jerusalemu pada. 10 Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa. 11 Ẹ fà sẹhin, é fà sẹhin, é jade kuro lãrin rẹ̀; ẹ má fọwọ kàn ohun aimọ́ kan: ẹ kuro lãrin rẹ̀, ẹ jẹ mimọ́, ẹnyin ti ngbe ohun-èlo Oluwa. 12 Nitori ẹ kì yio yara jade, bẹ̃ni ẹ kì yio fi isare lọ; nitori Oluwa yio ṣãju nyin; Ọlọrun Israeli yio si kó nyin jọ.

Iranṣẹ tí Ń Jìyà

13 Kiyesi i, iranṣẹ mi yio fi oye bá ni lò; a o gbe e ga, a o si gbe e leke, on o si ga gidigidi. 14 Gẹgẹ bi ẹnu rẹ ti yà ọ̀pọlọpọ enia, a bà oju rẹ̀ jẹ ju ti ẹnikẹni lọ, ati irisi rẹ̀ ju ti ọmọ enia lọ. 15 Bẹ̃ni yio buwọ́n ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède; awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ si i, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ́ ni nwọn o rò.

Isaiah 53

1 TALI o ti gbà ihìn wa gbọ́? tali a si ti fi apá Oluwa hàn fun? 2 Nitori yio dàgba niwaju rẹ̀ bi ọ̀jẹlẹ ohun ọ̀gbin, ati bi gbòngbo lati inu ilẹ gbigbẹ: irísi rẹ̀ kò dara, bẹ̃ni kò li ẹwà, nigbati a ba si ri i, kò li ẹwà ti a ba fi fẹ ẹ. 3 A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si. 4 Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju. 5 Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da. 6 Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀. 7 A jẹ ẹ ni iyà, a si pọ́n ọ loju, ṣugbọn on kò yà ẹnu rẹ̀: a mu u wá bi ọdọ-agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olurẹ́run rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀. 8 A mu u jade lati ibi ihamọ on idajọ: tani o si sọ iran rẹ̀? nitori a ti ke e kuro ni ilẹ alãye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u. 9 O si ṣe ibojì rẹ̀ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ̀ ni ikú rẹ̀; nitori kò hù iwà-ipa, bẹ̃ni kò si arekereke li ẹnu rẹ̀. 10 Ṣugbọn o wu Oluwa lati pa a lara; o ti fi i sinu ibanujẹ; nigbati iwọ o fi ẹmi rẹ̀ ṣẹbọ fun ẹ̀ṣẹ: yio ri iru-ọmọ rẹ̀, yio mu ọjọ rẹ̀ gùn, ifẹ Oluwa yio ṣẹ li ọwọ́ rẹ̀. 11 Yio ri ninu eso lãlã ọkàn rẹ̀, yio si tẹ́ ẹ li ọrùn: nipa imọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi olododo yio da ọ̀pọlọpọ lare; nitori yio rù aiṣedede wọn wọnni. 12 Nitorina emi o fun u ni ipín pẹlu awọn ẹni-nla, yio si ba awọn alagbara pín ikogun, nitori o ti tú ẹmi rẹ̀ jade si ikú: a si kà a mọ awọn alarekọja, o si rù ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ; o si nṣipẹ̀ fun awọn alarekọja.

Isaiah 54

Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli

1 KỌRIN, iwọ àgan, ti kò bi ri; bú si orin, si ké rara, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni-alahoro pọ̀ ju awọn ọmọ ẹniti a gbe ni iyawo: li Oluwa wi. 2 Sọ ibi agọ rẹ di gbigbõro, si jẹ ki wọn nà aṣọ tita ibugbe rẹ̀ jade: máṣe dási, sọ okùn rẹ di gigùn, ki o si mu ẽkàn rẹ le. 3 Nitori iwọ o ya si apa ọtún ati si apa osì, iru-ọmọ rẹ yio si jogun awọn keferi: nwọn o si mu ki awọn ilu ahoro wọnni di ibi gbigbe. 4 Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ. 5 Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e. 6 Nitori Oluwa ti pè ọ bi obinrin ti a kọ̀ silẹ, ti a si bà ni inu jẹ, ati bi aya igba ewe nigbati a ti kọ̀ ọ, li Ọlọrun rẹ wi. 7 Ni iṣẹju diẹ ni mo ti kọ̀ ọ silẹ, ṣugbọn li ãnu nla li emi o kó ọ jọ: 8 Ni ṣiṣàn ibinu li emi pa oju mi mọ kuro lara rẹ ni iṣẹju kan! ṣugbọn õre ainipẹkun li emi o fi ṣãnu fun ọ; li Oluwa Olurapada rẹ wí. 9 Nitori bi awọn omi Noa li eyi ri si mi, nitori gẹgẹ bi mo ti bura pe omi Noa kì yio bò aiye mọ, bẹ̃ni mo si ti bura pe emi kì yio binu si ọ, bẹ̃ni emi kì yio ba ọ wi. 10 Nitori awọn oke-nla yio ṣi lọ, a o si ṣi awọn oke kékèké ni idi, ṣugbọn ore mi kì yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni emi kì yio ṣi majẹmu alafia mi ni ipò: li Oluwa wi, ti o ṣãnu fun ọ.

Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu

11 Iwọ ẹniti a npọ́n loju, ti a si nfi ijì gbákiri, ti a kò si tù ninu, wò o, emi o fi tìrõ tẹ́ okuta rẹ, emi o si fi safire fi ipilẹ rẹ le ilẹ. 12 Emi o fi rubi ṣe ṣonṣo-ile rẹ, emi o si fi okuta didán ṣe àsẹ rẹ; emi o si fi awọn okuta àṣayan ṣe agbègbe rẹ. 13 A o si kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa wá; alafia awọn ọmọ rẹ yio si pọ̀. 14 Ninu ododo li a o fi idi rẹ mulẹ: iwọ o jina si inira; nitori iwọ kì yio bẹ̀ru: ati si ifoiya, nitori kì yio sunmọ ọ. 15 Kiye si i, ni kikojọ nwọn o kó ara wọn jọ, ṣugbọn ki iṣe nipasẹ mi; ẹnikẹni ti o ba ditẹ si ọ yio ṣubu nitori rẹ. 16 Kiye si i, emi li ẹniti o ti dá alagbẹ̀dẹ ti nfẹ́ iná ẹyín, ti o si mu ohun-elò jade fun iṣẹ rẹ̀; emi li o si ti dá apanirun lati panirun. 17 Kò si ohun-ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan; ati gbogbo ahọn ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ o da li ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa, lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá, li Oluwa wi.

Isaiah 55

Àánú Ọlọrun

1 NJẸ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ; lõtọ, ẹ wá, ẹ rà ọti-waini ati wàra, laini owo ati laidiyele. 2 Nitori kini ẹ ṣe nná owo fun eyiti kì iṣe onjẹ? ati lãla nyin fun eyi ti kì itẹnilọrun? ni gbigbọ́, ẹ gbọ́ t'emi, ki ẹ si jẹ eyi ti o dara, si jẹ ki inu nyin dùn ninu ọra. 3 Ẹ tẹtilelẹ, ki ẹ si wá sọdọ mi: ẹ gbọ́, ọkàn nyin yio si yè: emi o si ba nyin dá majẹmu ainipẹkun, ãnu Dafidi ti o daju. 4 Kiye si i, emi ti fi on fun awọn enia fun ẹlẹri, olori ati alaṣẹ fun awọn enia. 5 Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀, ati orilẹ-ède ti kò mọ̀ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israeli; nitori on ti ṣe ọ li ogo. 6 Ẹ wá Oluwa nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosí. 7 Jẹ ki enia buburu kọ̀ ọ̀na rẹ̀ silẹ, ki ẹ̀lẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ. 8 Nitori èro mi kì iṣe èro nyin, bẹ̃ni ọ̀na nyin kì iṣe ọ̀na mi, li Oluwa wi. 9 Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹ̃ni ọ̀na mi ga ju ọ̀na nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ. 10 Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun: 11 Bẹ̃ni ọ̀rọ mi ti o ti ẹnu mi jade yio ri: kì yio pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yio ṣe eyiti o wù mi, yio si ma ṣe rere ninu ohun ti mo rán a. 12 Nitori ayọ̀ li ẹ o fi jade, alafia li a o fi tọ́ nyin: awọn oke-nla ati awọn oke kékèké yio bú si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ́ yio si ṣapẹ́. 13 Igi firi yio hù jade dipò ẹgún, igi mirtili yio hù jade dipò oṣuṣu: yio si jẹ orukọ fun Oluwa, fun àmi aiyeraiye, ti a kì yio ke kuro.

Isaiah 56

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun

1 BAYI li Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ẹ si ṣe ododo: nitori igbala mi fẹrẹ idé, ati ododo mi lati fi hàn. 2 Alabukun ni fun ọkunrin na ti o ṣe eyi, ati fun ọmọ enia ti o dì i mu: ti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́; ti o si pa ọwọ́ rẹ̀ mọ kuro ni ṣiṣe ibi. 3 Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi. 4 Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ìwẹfa ti nwọn pa ọjọ isimi mi mọ, ti nwọn si yàn eyi ti o wù mi, ti nwọn si di majẹmu mi mu; 5 Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro. 6 Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu; 7 Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia. 8 Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.

A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli Lẹ́bi

9 Gbogbo ẹnyin ẹranko igbẹ, ẹ wá lati pajẹ ani gbogbo ẹranko igbẹ. 10 Afọju li awọn alore rẹ̀: òpe ni gbogbo wọn, odi ajá ni nwọn, nwọn kò le igbó, nwọn a ma sùn, nwọn ndubulẹ, nwọn fẹ ma tõgbé. 11 Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá. 12 Ẹ wá, ni nwọn wi, emi o mu ọti-waini wá, a o si mu ọti-lile li amuyo; ọla yio si dabi ọjọ oni, yio si pọ̀ lọpọlọpọ.

Isaiah 57

OLUWA dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli Lẹ́bi

1 OLODODO ṣegbe, kò si ẹniti o kà a si: a mu awọn alãnu kuro, kò si ẹniti nrò pe a mu olododo kuro ṣaju ibi. 2 On wọ̀ inu alafia: nwọn simi lori akete wọn, olukuluku ẹniti nrin ninu iduroṣinṣin rẹ̀. 3 Ṣugbọn ẹ sunmọ ihin, ẹnyin ọmọ oṣo, iru-ọmọ panṣaga on àgbere. 4 Tani ẹnyin fi nṣe ẹsín? tani ẹnyin nyanu gborò si, ti ẹnyin yọ ahọn jade si? ọmọ alarekọja ki ẹnyin, iru-ọmọ eke, 5 Ti òriṣa ngùn labẹ gbogbo igi tutù, ti ẹ npa awọn ọmọ wẹrẹ ninu afonifoji wọnni, labẹ apáta ti o yanu? 6 Lãrin okuta ọ̀bọrọ́ odo ni ipín rẹ, awọn, awọn ni ipín rẹ: ani awọn ni iwọ dà ẹbọ ọrẹ mimu si: ti iwọ si rú ẹbọ ọrẹ jijẹ. Emi ha le gbà itunu ninu wọnyi? 7 Lori oke giga giga ni iwọ fi akete rẹ si, ani nibẹ ni iwọ ti lọ lati rú ẹbọ. 8 Lẹhin ilẹkùn ati opó ilẹkun ni iwọ si ti gbe iranti rẹ soke: nitori iwọ ti fi ara rẹ hàn fun ẹlomiran dipò mi, iwọ si ti goke: iwọ ti sọ akete rẹ di nla, iwọ si ba wọn dá majẹmu; iwọ ti fẹ akete wọn nibiti iwọ ri i. 9 Iwọ si ti lọ tiwọ ti ikunra sọdọ ọba, iwọ si ti sọ õrùn didùn rẹ di pupọ, iwọ si ti rán awọn ikọ̀ rẹ lọ jina réré, iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ, ani si ipò okú. 10 Ãrẹ̀ mu ọ ninu jijìn ọ̀na rẹ: iwọ kò wipe, Ireti kò si: ìye ọwọ́ rẹ ni iwọ ti ri; nitorina ni inu rẹ kò ṣe bajẹ. 11 Ẹ̀ru tani mbà ọ ti o si nfòya, ti o nṣeke, ti iwọ kò si ranti mi tabi ki o kà a si? emi kò ha ti dakẹ ani lati igbãni wá, iwọ kò si bẹ̀ru mi? 12 Emi o fi ododo rẹ, ati iṣẹ rẹ hàn; nwọn kì o si gbè ọ. 13 Nigbati iwọ ba kigbe, jẹ ki awọn ẹgbẹ rẹ ki o gbà ọ; ṣugbọn ẹfũfu ni yio gbá gbogbo wọn lọ; emi yio mu wọn kuro: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹ rẹ̀ le mi yio ni ilẹ na, yio si jogun oke mimọ́ mi.

Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn

14 On o si wipe, Ẹ kọ bèbe, ẹ kọ bèbe, ẹ tun ọ̀na ṣe; ẹ mu ìdugbolu kuro li ọ̀na awọn enia mi. 15 Nitori bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti a gbéga soke sọ, ti ngbe aiyeraiye, orukọ ẹniti ijẹ Mimọ́, emi ngbe ibi giga ati mimọ́, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji. 16 Nitori emi kì yio jà titi lai, bẹ̃ni emi kì yio binu nigbagbogbo: nitori ẹmi iba daku niwaju mi, ati ẽmi ti emi ti dá. 17 Mo ti binu nitori aiṣedede ojukokoro rẹ̀, mo si lù u: mo fi oju pamọ́, mo si binu, on si nlọ ni iṣìna li ọ̀na ọkàn rẹ̀. 18 Mo ti ri ọ̀na rẹ̀, emi o si mu u li ara da: emi o si tọ́ ọ pẹlu, emi o si mu itunu pada fun u wá, ati fun awọn aṣọ̀fọ rẹ̀. 19 Emi li o da eso ète; Alafia, alafia fun ẹniti o jina rére, ati fun ẹniti o wà nitosí, ni Oluwa wi; emi o si mu u li ara da. 20 Ṣugbọn awọn enia buburu dabi okun ríru, nigbati kò le simi, eyiti omi rẹ̀ nsọ ẹrẹ ati ẽri soke. 21 Alafia kò si fun awọn enia buburu, ni Ọlọrun mi wi.

Isaiah 58

Ààwẹ̀ Tòótọ́

1 KE rara, máṣe dasi, gbe ohùn rẹ soke bi ipè, ki o si fi irekọja awọn enia mi hàn wọn, ati ile Jakobu, ẹ̀ṣẹ wọn. 2 Ṣugbọn nwọn nwá mi lojojumọ, nwọn si ni inu didun lati mọ̀ ọ̀na mi, bi orilẹ-ède ti nṣe ododo, ti kò si fi ilàna Ọlọrun wọn silẹ: nwọn mbere ilàna ododo wọnnì lọwọ mi; nwọn a ma ṣe inu didun ati sunmọ Ọlọrun. 3 Nitori kini awa ṣe ngbãwẹ̀, ti iwọ kò si ri i? nitori kini awa jẹ ọkàn wa ni ìya, ti iwọ kò si mọ̀? Kiyesi i, li ọjọ ãwẹ̀ nyin ẹnyin nṣe afẹ́, ẹ si nfi agbara mu ni ṣe gbogbo iṣẹ nyin. 4 Kiyesi i, ẹnyin ngbãwẹ̀ fun ìja ati ãwọ̀, ati lilù, nipa ikũku ìwa-buburu: ẹ máṣe gbãwẹ bi ti ọjọ yi, ki a le gbọ́ ohùn nyin li oke. 5 Ãwẹ̀ iru eyi ni mo yàn bi? ọjọ ti enia njẹ ọkàn rẹ̀ ni ìya? lati tẹ ori rẹ̀ ba bi koriko odo? ati lati tẹ́ aṣọ ọ̀fọ ati ẽru labẹ rẹ̀? iwọ o ha pe eyi ni ãwẹ̀, ati ọjọ itẹwọgba fun Oluwa? 6 Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga. 7 Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ. 8 Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ. 9 Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ. 10 Bi iwọ ba fà ọkàn rẹ jade fun ẹniti ebi npa, ti o si tẹ́ ọkàn ti a npọ́n loju lọrùn, nigbana ni imọlẹ rẹ yio si là ninu okùnkun, ati okùnkun rẹ bi ọ̀san gangan. 11 Oluwa yio ma tọ́ ọ nigbagbogbo, yio si tẹ́ ọkàn rẹ lọrun ni ibi gbigbẹ, yio si mu egungun rẹ sanra; iwọ o si dabi ọgbà ti a bomirin, ati bi isun omi ti omi rẹ̀ ki itán. 12 Ati awọn tirẹ yio mọ ibi ahoro atijọ wọnni: iwọ o gbé ipilẹ iran ọ̀pọlọpọ ró, a o si ma pe ọ ni, Alatunṣe ẹyà nì, Olumupada ọ̀na wọnni lati gbe inu rẹ̀.

Èrè Pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́

13 Bi iwọ ba yí ẹsẹ rẹ kuro li ọjọ isimi, lati má ṣe afẹ́ rẹ li ọjọ isimi mi; ti iwọ si pè ọjọ isimi ni adùn, ọjọ mimọ́ Oluwa, ọlọ́wọ̀; ti iwọ si bọ̀wọ fun u, ti iwọ kò hù ìwa rẹ, tabi tẹle afẹ rẹ, tabi sọ ọ̀rọ ara rẹ. 14 Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gùn ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ níni Jakobu baba rẹ bọ́ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ.

Isaiah 59

Wolii Lòdì sí Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Eniyan

1 KIYESI i, ọwọ́ Oluwa kò kuru lati gbàni, bẹ̃ni eti rẹ̀ kò wuwo ti kì yio fi gbọ́. 2 Ṣugbọn aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati ẹ̀ṣẹ nyin li o pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ nyin, ti on kì yio fi gbọ́. 3 Nitori ọwọ́ nyin di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ, ati ika nyin fun aiṣedede, ète nyin nsọ eke, ahọn nyin nsọ ibi jade. 4 Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun. 5 Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade. 6 Okùn wọn kì yio di ẹwù, bẹ̃ni nwọn kì yio fi iṣẹ wọn bò ara wọn: iṣẹ wọn ni iṣẹ ikà, iṣe ipá si mbẹ li ọwọ́ wọn. 7 Ẹsẹ wọn sare si ibi, nwọn si yara lati tajẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ: èro wọn èro ibi ni; ibajẹ ati iparun mbẹ ni ipa wọn. 8 Ọ̀na alafia ni nwọn kò mọ̀; kò si idajọ kan ninu ìrin wọn: nwọn ṣe ipa-ọ̀na wiwọ́ fun ara wọn: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ ọ kì yio mọ̀ alafia.

Àwọn Eniyan Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ wọn

9 Nitori na ni idajọ jìna si wa, bẹ̃ni ododo kì yio le wa bá, awa duro dè imọlẹ, ṣugbọn kiyesi i, okunkun, a duro de imọlẹ, ṣugbọn a nrin ninu okunkun. 10 A nwá ogiri kiri bi afọju, awa si nwá ọ̀na bi ẹniti kò li oju: awa nkọsẹ lọsangangan bi ẹnipe loru, ni ibi ahoro, bi okú. 11 Gbogbo wa mbu bi beari, awa si npohunrere bi oriri: awa wò ọ̀na fun idajọ, ṣugbọn kò si, fun igbala, ṣugbọn o jìna si wa. 12 Nitori irekọja wa npọ̀ si i niwaju rẹ, ẹ̀ṣẹ wa njẹri gbè wa, nitori irekọja wa mbẹ lọdọ wa, niti aiṣedede wa, awa mọ̀ wọn. 13 Ni rirekọja ati ṣiṣeke si Oluwa, ifaṣẹhin kuro lọdọ Ọlọrun wa, isọrọ inilara ati ìṣọtẹ, liloyun ati sisọrọ eke lati inu jade wá. 14 A dá idajọ pada, ẹtọ́ si duro lokerè rére: otitọ ṣubu ni igboro, aiṣègbe kò le wọ ile. 15 Otitọ kò si, ẹniti o si kuro ninu ibi o sọ ara rẹ̀ di ijẹ: Oluwa si ri i, o si buru loju rẹ̀, ti idajọ kò si.

OLUWA Ṣetán láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀

16 O si ri pe kò si ẹnikan, ẹnu si yà a pe onipẹ̀ kò si, nitorina apá rẹ̀ mu igbala fun u wá; ati ododo rẹ̀, on li o gbé e ró. 17 O si gbe ododo wọ̀ bi awo-aiya, o si fi aṣibori irin igbala dé ara rẹ̀ lori: o wọ̀ ẹwù igbẹsan li aṣọ, a si fi itara wọ̀ ọ bi agbada. 18 Gẹgẹ bi ere iṣe wọn, bẹ̃ gẹgẹ ni yio san a fun wọn, irunú fun awọn ọta rẹ̀, igbẹsan fun awọn ọta rẹ̀; fun awọn erekuṣu yio san ẹsan. 19 Nwọn o si bẹ̀ru orukọ Oluwa lati ìwọ-õrùn wá, ati ogo rẹ̀ lati ilà-õrun wá. Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i. 20 Olurapada yio si wá si Sioni, ati sọdọ awọn ti o yipada kuro ninu irekọja ni Jakobu, ni Oluwa wi. 21 Niti emi, eyi ni majẹmu mi pẹlu wọn, ni Oluwa wi; Ẹmi mi ti o wà lara rẹ̀, ati ọ̀rọ mi ti mo fi si ẹnu rẹ, kì yio kuro li ẹnu rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ ọmọ rẹ, ni Oluwa wi, lati isisiyi lọ ati lailai.

Isaiah 60

Ògo Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu

1 DIDE, tàn imọlẹ: nitori imọlẹ rẹ dé, ogo Oluwa si yọ lara rẹ. 2 Nitori kiyesi i, okùnkun bò aiye mọlẹ, ati okùnkun biribiri bò awọn enia: ṣugbọn Oluwa yio yọ lara rẹ, a o si ri ogo rẹ̀ lara rẹ. 3 Awọn keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ. 4 Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ. 5 Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ. 6 Ọ̀pọlọpọ rakunmi yio bò ọ mọlẹ, awọn ọmọ rakunmi Midiani on Ẹfa; gbogbo wọn o wá lati Ṣeba: nwọn o mu wura ati turari wá; nwọn o fi iyìn Oluwa hàn sode. 7 A o ṣà gbogbo ọwọ́-ẹran Kedari jọ sọdọ rẹ, awọn àgbo Nebaioti yio ṣe iranṣẹ fun ọ; nwọn o goke wá si pẹpẹ mi pẹlu itẹwọgba, emi o si ṣe ile ogo mi li ogo. 8 Tani wọnyi ti nfò bi awọsanma, ati bi awọn ẹiyẹle si ojule wọn? 9 Nitõtọ erekuṣu wọnni yio duro dè mi, ọkọ Tarṣiṣi wọnni li ekini, lati mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti ọ̀na jìjin wá, fadaka wọn, ati wura wọn pẹlu wọn, fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ, ati fun Ẹni-Mimọ́ Israeli, nitoriti on ti ṣe ọ logo. 10 Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ìkannu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣãnu fun ọ. 11 Nitori na awọn ẹnu-bodè rẹ yio ṣi silẹ nigbagbogbo; a kì yio se wọn lọsan tabi loru, ki a le mu ọla awọn Keferi wá sọdọ rẹ, ki a ba si mu awọn ọba wọn wá. 12 Nitori orilẹ-ède, tabi ilẹ ọba ti kì yio sin ọ, yio ṣegbe; orilẹ-ède wọnni li a o sọ dahoro raurau. 13 Ogo Lebanoni yio wá sọdọ rẹ, igi firi, igi pine, pẹlu igi boksi, lati ṣe ibi mimọ́ mi li ọṣọ; emi o ṣe ibi ẹsẹ mi logo. 14 Awọn ọmọkunrin awọn aninilara rẹ pẹlu yio wá ni itẹriba sọdọ rẹ; gbogbo awọn ti o ti ngàn ọ, nwọn o tẹ̀ ara wọn ba silẹ li atẹlẹsẹ rẹ; nwọn o si pe ọ ni Ilu Oluwa, Sioni ti Ẹni-Mimọ́ Israeli. 15 Ni bi a ti kọ̀ ọ silẹ, ti a si ti korira rẹ, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja lãrin rẹ, emi o sọ ọ di ogo aiyeraiye, ayọ̀ iran-de-iran ọ̀pọlọpọ. 16 Iwọ o mu wàra awọn Keferi, iwọ o si mu ọmu awọn ọba; iwọ o si mọ̀ pe, emi Oluwa ni Olugbala rẹ, ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara Jakobu. 17 Nipo idẹ emi o mu wura wá, nipo irin emi o mu fadaka wá, ati nipo igi, idẹ, ati nipo okuta, irin: emi o ṣe awọn ijoye rẹ ni alafia, ati awọn akoniṣiṣẹ́ rẹ ni ododo. 18 A kì yio gbọ́ ìwa-ipá mọ ni ilẹ rẹ, idahoro tabi iparun li agbègbe rẹ; ṣugbọn iwọ o pe odi rẹ ni Igbala, ati ẹnu-bodè rẹ ni Iyin. 19 Õrùn kì yio jẹ imọlẹ rẹ mọ li ọsan, bẹ̃ni oṣupa kì yio fi imọlẹ rẹ̀ ràn fun ọ; ṣugbọn Oluwa yio ṣe imọlẹ ainipẹkun rẹ, ati Ọlọrun rẹ ogo rẹ. 20 Õrùn rẹ ki yio wọ̀ mọ; bẹ̃ni oṣupa rẹ kì yio wọ̃kùn: nitori Oluwa yio jẹ imọlẹ ainipẹkun fun ọ, ọjọ ãwẹ̀ rẹ wọnni yio si de opin. 21 Ati awọn enia rẹ, gbogbo wọn o jẹ olododo: nwọn o jogun ilẹ na titi lailai, ẹka gbigbin mi, iṣẹ ọwọ́ mi, ki a ba le yìn mi logo. 22 Ẹni-kekere kan ni yio di ẹgbẹrun, ati kekere kan yio di alagbara orilẹ-ède: emi Oluwa yio ṣe e kankan li akokò rẹ̀.

Isaiah 61

Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè

1 ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè. 2 Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu. 3 Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo. 4 Nwọn o si mọ ibi ahoro atijọ wọnni, nwọn o gbe ahoro atijọ wọnni ro, nwọn o si tun ilu wọnni ti o ṣofo ṣe, ahoro iran ọ̀pọlọpọ. 5 Awọn alejò yio si duro, nwọn o si bọ́ ọwọ́ ẹran nyin, awọn ọmọ alejò yio si ṣe atulẹ nyin, ati olurẹ́ ọwọ́ àjara nyin. 6 Ṣugbọn a o ma pè nyin ni Alufa Oluwa: nwọn o ma pè nyin ni Iranṣẹ Ọlọrun wa: ẹ o jẹ ọrọ̀ wọn Keferi, ati ninu ogo awọn li ẹ o mã ṣogo. 7 Nipo itijú nyin ẹ o ni iṣẹpo-meji; ati nipo idãmu, nwọn o yọ̀ ninu ipin wọn: nitorina nwọn o ni iṣẹpo-meji ni ilẹ wọn: ayọ̀ ainipẹkun yio jẹ ti wọn. 8 Nitori emi Oluwa fẹ idajọ, mo korira ijale ninu aiṣododo; emi o si fi iṣẹ wọn fun wọn ni otitọ, emi o si ba wọn da majẹmu aiyeraiye. 9 A o si mọ̀ iru wọn ninu awọn Keferi, ati iru-ọmọ wọn lãrin awọn enia, gbogbo ẹniti o ri wọn yio mọ̀ wọn, pé, iru-ọmọ ti Oluwa busi ni nwọn. 10 Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yio yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi agbáda wọ̀ mi, o ti fi aṣọ ododo bò mi, gẹgẹ bi ọkọ iyawó ti iṣe ara rẹ̀ lọṣọ́, ati bi iyawó ti ifi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọṣọ́. 11 Nitori gẹgẹ bi ilẹ ti imu ẽhù rẹ̀ jade, ati bi ọgbà ti imu ohun ti a gbìn sinu rẹ̀ hù soke; bẹ̃ni Oluwa Jehofah yio mu ododo ati iyìn hù soke niwaju gbogbo orilẹ-ède.

Isaiah 62

1 NITORI ti Sioni emi kì yio dakẹ, ati nitori ti Jerusalemu emi kì yio simi, titi ododo rẹ̀ yio fi jade bi titan imọlẹ, ati igbala rẹ̀ bi fitila ti njó. 2 Ati awọn Keferi yio ri ododo rẹ, ati gbogbo ọba yio ri ogo rẹ: a o si fi orukọ titun pè ọ, eyiti ẹnu Oluwa yio darukọ. 3 Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ. 4 A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo. 5 Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti igbé wundia ni iyawo, bẹ̃ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio gbe ọ ni iyawo: ati bi ọkọ iyawo ti iyọ̀ si iyawo, bẹ̃ni Ọlọrun rẹ yio yọ̀ si ọ. 6 Emi ti fi awọn alore sori odi rẹ, iwọ Jerusalemu, ti kì yio pa ẹnu wọn mọ lọsan ati loru titilai: ẹnyin ti nṣe iranti Oluwa, ẹ máṣe dakẹ. 7 Ẹ máṣe fun u ni isimi, titi yio fi fi idi Jerusalemu mulẹ, ti yio ṣe e ni iyìn li aiye. 8 Oluwa ti fi apá ọtun rẹ̀, ati apá agbara rẹ̀ bura, Lõtọ emi kì yio fi ọkà rẹ ṣe onjẹ fun awọn ọta rẹ mọ, bẹ̃ni awọn ọmọ ajeji kì yio mu ọti-waini rẹ, eyi ti iwọ ti ṣíṣẹ fun. 9 Ṣugbọn awọn ti o ṣà a jọ yio jẹ ẹ, nwọn o si yìn Oluwa; ati awọn ti nkó o jọ yio mu u, ninu ãfin mimọ́ mi. 10 Ẹ kọja lọ, ẹ kọja li ẹnu bode; tun ọ̀na awọn enia ṣe; kọ bèbe, kọ bèbe opopo; ṣà okuta wọnni kuro, gbe ọpagun ró fun awọn enia. 11 Kiyesi i, Oluwa ti kede titi de opin aiye: Ẹ wi fun ọmọbinrin Sioni pe, Wo o, igbala rẹ de; wo o, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ati ẹsan rẹ̀ niwaju rẹ̀. 12 A o si ma pè wọn ni, Enia mimọ́, Ẹni-irapada Oluwa: a o si ma pè ọ ni, Iwári, Ilu aikọ̀silẹ.

Isaiah 63

Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè

1 TANI eleyi ti o ti Edomu wá, ti on ti aṣọ arẹpọ́n lati Bosra wá? eyi ti o li ogo ninu aṣọ rẹ̀, ti o nyan ninu titobi agbara rẹ̀? Emi ni ẹniti nsọ̀rọ li ododo, ti o ni ipá lati gbala. 2 Nitori kini aṣọ rẹ fi pọ́n, ti aṣọ rẹ wọnni fi dabi ẹniti ntẹ̀ ohun-èlo ifunti waini? 3 Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n. 4 Nitori ọjọ ẹsan mbẹ li aiya mi, ọdun awọn ẹni-irapada mi ti de. 5 Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro. 6 Emi si tẹ̀ awọn enia mọlẹ ninu ibinu mi, mo si mu wọn mu yó ninu irunú mi, mo si mu ipa wọn sọkalẹ si ilẹ.

Oore OLUWA sí Israẹli

7 Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀. 8 On si wipe, Lõtọ enia mi ni nwọn, awọn ọmọ ti kì iṣeke: on si di Olugbala wọn. 9 Ninu gbogbo ipọnju wọn, oju a pọn ọ, angeli iwaju rẹ̀ si gbà wọn: ninu ifẹ rẹ̀ ati suru rẹ̀ li o rà wọn pada; o si gbe wọn, o si rù wọn ni gbogbo ọjọ igbani. 10 Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ, nwọn si bi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ ninu; nitorina li o ṣe pada di ọta wọn, on tikalarẹ̀ si ba wọn ja. 11 Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà? 12 Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀? 13 Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ? 14 Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.

Adura fún Àánú ati Ìrànlọ́wọ́

15 Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi? 16 Laiṣiyemeji iwọ ni baba wa, bi Abrahamu tilẹ ṣe alaimọ̀ wa, ti Israeli kò si jẹwọ wa: iwọ Oluwa, ni baba wa, Olurapada wa; lati aiyeraiye ni orukọ rẹ. 17 Oluwa, nitori kili o ṣe mu wa ṣina kuro li ọ̀na rẹ, ti o si sọ ọkàn wa di lile kuro ninu ẹ̀ru rẹ? Yipada nitori awọn iranṣẹ rẹ, awọn ẹya ilẹ ini rẹ. 18 Awọn enia mimọ́ rẹ ti ni i, ni igba diẹ: awọn ọta wa ti tẹ̀ ibi mimọ́ rẹ mọlẹ. 19 Tirẹ li awa: lati lailai iwọ kò jọba lori wọn, a kò pè orukọ rẹ mọ wọn.

Isaiah 64

1 IWỌ iba jẹ fà awọn ọrun ya, ki iwọ si sọkalẹ, ki awọn oke-nla ki o le yọ́ niwaju rẹ. 2 Gẹgẹ bi igbati iná ileru ti njo, bi iná ti imu omi hó, lati sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun awọn ọta rẹ, ki awọn orilẹ-ède ki o le warìri niwaju rẹ! 3 Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ. 4 Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e. 5 Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là? 6 Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ. 7 Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa. 8 Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ. 9 Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe. 10 Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro. 11 Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run. 12 Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla?

Isaiah 65

Ìyà tí Ọlọrun yóo fi Jẹ Àwọn Ọlọ̀tẹ̀

1 A wá mi lọdọ awọn ti kò bere mi; a ri mi lọdọ awọn ti kò wá mi: mo wi fun orilẹ-ède ti a kò pe li orukọ mi pe, Wò mi, wò mi. 2 Ni gbogbo ọjọ ni mo ti na ọwọ́ mi si awọn ọlọtẹ̀ enia, ti nrìn li ọ̀na ti kò dara, nipa ìro ara wọn; 3 Awọn enia ti o nṣọ́ mi ni inu nigbagbogbo kàn mi loju; ti nrubọ ninu agbàla, ti nwọn si nfi turari jona lori pẹpẹ briki. 4 Awọn ti ngbe inu ibojì, ti nwọn si nwọ̀ ni ile awọn oriṣa, ti njẹ ẹran ẹlẹdẹ, omi-ẹran nkan irira si mbẹ ninu ohun-elò wọn; 5 Ẹniti o wipe, Duro fun ara rẹ, máṣe sunmọ mi; nitori ti mo ṣe mimọ́ jù ọ lọ. Wọnyi li ẹ̃fin ni imu mi, iná ti njo ni gbogbo ọjọ ni. 6 Kiyesi i, a ti kọwe rẹ̀ niwaju mi: emi kì o dakẹ, ṣugbọn emi o gbẹ̀san, ani ẹ̀san si aiya wọn, 7 Aiṣedede nyin, ati aiṣedede awọn baba nyin ṣọkan pọ̀, li Oluwa wi, awọn ẹniti o fi turari jona lori oke-nla, ti nwọn mbu ọla mi kù lori awọn oke kékèké: nitori na li emi o wọ̀n iṣẹ wọn iṣaju, sinu aiya wọn. 8 Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run. 9 Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ. 10 Ṣaroni yio di agbo-ẹran, ati afonifoji Akori ibikan fun awọn ọwọ́ ẹran lati dubulẹ ninu rẹ̀, nitori awọn enia mi ti o ti wá mi kiri. 11 Ṣugbọn ẹnyin ti o kọ̀ Oluwa silẹ, ti o gbàgbe oke-nla mimọ́ mi, ti o pèse tabili fun Gadi, ti o si fi ọrẹ mimu kun Meni. 12 Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si. 13 Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin: 14 Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn. 15 Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran: 16 Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.

Ayé Tuntun

17 Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya. 18 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rẹ̀ ni ayọ̀. 19 Emi o si ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o si yọ̀ ninu awọn enia mi: a kì yio si tun gbọ́ ohùn ẹkún mọ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe. 20 Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu. 21 Nwọn o si kọ ile, nwọn o si gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgba àjara, nwọn o si jẹ eso wọn. 22 Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn. 23 Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn. 24 Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahùn; ati bi nwọn ba ti nsọ̀rọ lọwọ, emi o gbọ́. 25 Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ̀, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-mãlu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn kì yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi, li Oluwa wi.

Isaiah 66

OLUWA Dá àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́

1 BAYI ni Oluwa wi, pe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si ni apoti itisẹ̀ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ́ fun mi gbé wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà? 2 Nitori gbogbo nkan wọnni li ọwọ́ mi sa ti ṣe, gbogbo nkan wọnni si ti wà, li Oluwa wi: ṣugbọn eleyi li emi o wò, ani òtoṣi ati oniròbinujẹ ọkàn, ti o si nwarìri si ọ̀rọ mi.

Kò Ṣeku kò Ṣẹyẹ

3 Ẹniti o pa akọ-malu, o dabi ẹnipe o pa enia; ẹniti o fi ọdọ-agutan rubọ, a dabi ẹnipe o bẹ́ ajá lọrùn; ẹniti o rubọ ọrẹ, bi ẹnipe o fi ẹ̀jẹ ẹlẹdẹ̀ rubọ; ẹniti o fi turari jona, bi ẹniti o sure fun òriṣa. Nitotọ, nwọn ti yàn ọ̀na ara wọn, inu wọn si dùn si ohun iríra wọn. 4 Emi pẹlu yio yàn itanjẹ wọn, emi o si mu eyi ti nwọn bẹ̀ru wá sara wọn, nitori nigbati mo pè, kò si ẹnikan ti o dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, nwọn kò gbọ́: ṣugbọn nwọn ṣe buburu niwaju mi, nwọn si yàn eyiti inu mi kò dùn si. 5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na. 6 Ohùn ariwo lati inu ilu wá, ohùn lati inu tempili wá, ohùn Oluwa ti nsan ẹ̀san fun awọn ọta rẹ̀. 7 Ki o to rọbi, o bimọ; ki irora rẹ̀ ki o to de, o bi ọmọkunrin kan. 8 Tali o ti igbọ́ iru eyi ri? tali o ti iri irú eyi ri? Ilẹ le hù nkan jade li ọjọ kan bi? tabi a ha le bi orilẹ-ède ni ọjọ́ kan nã? nitori bi Sioni ti nrọbi gẹ, bẹ̃li o bi awọn ọmọ rẹ̀. 9 Emi o ha mu wá si irọbi, ki nmá si mu ki o bi? li Oluwa wi: emi o ha mu ni bi, ki nsi sé inu? li Ọlọrun rẹ wi. 10 Ẹ ba Jerusalemu yọ̀, ki inu nyin si dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹnyin ti o fẹ ẹ; ẹ ba a yọ̀ fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti ngbãwẹ̀ fun u. 11 Ki ẹnyin ki o le mu ọmú, ki a si fi ọmú itunu rẹ̀ tẹ́ nyin lọrùn; ki ẹnyin ki o ba le fun wàra, ki inu nyin ba sì le dùn si ọ̀pọlọpọ ogo rẹ̀. 12 Nitori bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o nà alafia si i bi odò, ati ogo awọn Keferi bi odò ṣiṣàn: nigbana li ẹnyin o mu ọmú, a o dà nyin si ẹgbẹ́ rẹ̀, a o si ma gbe nyin jo lori ẽkún rẹ̀. 13 Gẹgẹ bi ẹniti iya rẹ̀ ntù ninu, bẹ̃ni emi o tù nyin ninu; a o si tù nyin ninu ni Jerusalemu. 14 Nigbati ẹnyin ba ri eyi, ọkàn nyin yio yọ̀, egungun nyin yio si tutu yọ̀yọ bi ewebẹ̀; a o si mọ̀ ọwọ́ Oluwa lara awọn iranṣẹ rẹ̀, ati ibinu rẹ̀ si awọn ọta rẹ̀. 15 Nitori kiyesi i, Oluwa mbọ wá ti on ti iná, ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀ bi ãjà, lati fi irunu sẹsan ibinu rẹ̀, ati ibawi rẹ̀ nipa ọwọ́ iná. 16 Nitori Oluwa yio fi iná ati idà rẹ̀ ṣe idajọ gbogbo ẹran-ara; awọn okú Oluwa yio si pọ̀. 17 Awọn ti o yà ara wọn si mimọ́, ti nwọn si sọ ara wọn di mimọ́ ninu agbala wọnni, ti ọkan tẹle ekeji li ãrin, nwọn njẹ ẹran ẹlẹdẹ, ati ohun irira, ati eku, awọn li a o parun pọ̀; li Oluwa wi. 18 Nitori emi mọ̀ iṣẹ ati ìro wọn: igba na yio dé lati ṣà gbogbo awọn orilẹ-ède ati ahọn jọ, nwọn o si wá, nwọn o si ri ogo mi. 19 Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi. 20 Nwọn o si mu gbogbo awọn arakunrin nyin lati orilẹ-ède gbogbo wá, ẹbọ kan si Oluwa lori ẹṣin, ati ninu kẹkẹ́, ati ninu páfa, ati lori ibaka, ati lori rakunmi, si Jerusalemu oke-nla mimọ́ mi; li Oluwa wi, gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti imu ọrẹ wá ninu ohun-elò mimọ́ sinu ile Oluwa. 21 Ninu wọn pẹlu li emi o si mu ṣe alufa ati Lefi; li Oluwa wi. 22 Nitori gẹgẹ bi awọn ọrun titun, ati aiye titun, ti emi o ṣe, yio ma duro niwaju mi, bẹ̃ni iru-ọmọ rẹ ati orukọ rẹ yio duro, li Oluwa wi. 23 Yio si ṣe, gbogbo ẹran-ara yio si wá tẹriba niwaju mi, lati oṣù titun de oṣù titun, ati lati ọjọ isimi de ọjọ isimi, li Oluwa wi. 24 Nwọn o si jade lọ, nwọn o si wò okú awọn ti o ti ṣọtẹ si mi: nitori kokoro wọn kì yio kú, bẹ̃ni iná wọn kì yio si kú; nwọn o si jẹ ohun irira si gbogbo ẹran-ara.

Jeremiah 1

1 Ọ̀RỌ Jeremiah, ọmọ Hilkiah, ọkan ninu awọn alufa ti o wà ni Anatoti, ni ilẹ Benjamini. 2 Ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá ni igba ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, li ọdun kẹtala ijọba rẹ̀. 3 O si tọ̀ ọ wá pẹlu ni igba ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, titi de opin ọdun kọkanla Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, ani de igba ti a kó Jerusalemu lọ ni igbekun li oṣu karun.

Ọlọrun Pe Jeremiah

4 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe: 5 Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède. 6 Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi. 7 Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ. 8 Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi. 9 Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu. 10 Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn.

Ìran Meji

11 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Jeremiah, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ọpa igi almondi. 12 Oluwa si wi fun mi pe, iwọ riran rere, nitori ti emi o kiye si ọ̀rọ mi lati mu u ṣẹ. 13 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá lẹ̃keji pe, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ìkoko ori iná, oju rẹ̀ si ni lati iha ariwa wá. 14 Nigbana ni Oluwa sọ fun mi pe, ibi yio tú jade lati ariwa wá, sori gbogbo awọn ti ngbe inu ilẹ. 15 Sa wò o, Emi o pè gbogbo idile awọn ijọba ariwa, li Oluwa wi, nwọn o si wá: olukuluku wọn o si tẹ́ itẹ rẹ̀ li ẹnu-bode Jerusalemu, ati lori gbogbo odi rẹ̀ yikakiri, ati lori gbogbo ilu Juda. 16 Emi o si sọ̀rọ idajọ mi si wọn nitori gbogbo buburu wọn; ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ti nwọn si tẹriba fun iṣẹ ọwọ wọn. 17 Ṣugbọn iwọ di ẹ̀gbẹ́ rẹ li amure, ki o si dide, ki o si wi fun wọn gbogbo ohun ti emi o pa laṣẹ fun ọ, má fòya niwaju wọn, ki emi ki o má ba mu ọ dãmu niwaju wọn. 18 Sa wò o, loni ni mo fi ọ ṣe ilu-odi, ati ọwọ̀n irin, ati odi idẹ fun gbogbo ilẹ; fun awọn ọba Juda, awọn ijoye rẹ̀, awọn alufa, ati enia ilẹ na. 19 Ṣugbọn nwọn o ba ọ jà, nwọn kì o si le bori rẹ; nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ.

Jeremiah 2

Ìtọ́jú Ọlọrun lórí Israẹli

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, 2 Lọ, ki o si ke li eti Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ranti rẹ, iṣeun igbà ọmọde rẹ, ifẹ igbeyawo rẹ, nigbati iwọ tẹle mi ni iju, ni ilẹ ti a kì igbin si. 3 Mimọ́ ni Israeli fun Oluwa, akọso eso oko rẹ̀, ẹnikẹni ti o fi jẹ yio jẹbi; ibi yio si wá si ori wọn, li Oluwa wi.

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Baba Ńlá Israẹli

4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ara-ile Jakobu, ati gbogbo iran ile Israeli: 5 Bayi li Oluwa wi: Aiṣedede wo li awọn baba nyin ri lọwọ mi ti nwọn lọ jina kuro lọdọ mi, ti nwọn si tẹle asan, ti nwọn si di enia asan? 6 Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si. 7 Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira: 8 Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè.

OLUWA fi Ẹ̀sùn Kan Àwọn Eniyan Rẹ̀

9 Nitorina, Emi o ba nyin jà, li Oluwa wi, Emi o si ba atọmọde-ọmọ nyin jà. 10 Njẹ, ẹ kọja lọ si erekuṣu awọn ara Kittimu, ki ẹ si wò, si ranṣẹ lọ si Kedari, ki ẹ si ṣe akiyesi gidigidi, ki ẹ wò bi iru nkan yi ba mbẹ nibẹ? 11 Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè. 12 Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi! 13 Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.

Èrè Aiṣododo Israẹli

14 Ẹrú ni Israeli iṣe bi? tabi ẹru ibile? ẽṣe ti o fi di ijẹ. 15 Awọn ọmọ kiniun ke ramuramu lori rẹ̀, nwọn si bú, nwọn si sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ilu rẹ̀ li a fi jona li aini olugbe. 16 Awọn ọmọ Nofi ati ti Tafanesi pẹlu ti jẹ agbari rẹ; 17 Fifi Oluwa ọlọrun rẹ silẹ kọ́ ha mu eyi ba ọ, nigbati o tọ́ ọ loju ọ̀na? 18 Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀. 19 Ìwa-buburu rẹ ni yio kọ́ ọ, ipadasẹhin rẹ ni yio si ba ọ wi: mọ̀, ki iwọ si ri i pe, ohun buburu ati kikoro ni, pe, iwọ ti kò Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe ìbẹru mi kò si si niwaju rẹ; li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi.

Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA

20 Nitori ni igba atijọ iwọ ti ṣẹ́ ajaga ọrun rẹ, iwọ si já idè rẹ; iwọ si wipe, Emi kì o sìn, nitori lori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo ni iwọ nṣe panṣaga. 21 Ṣugbọn emi ti gbin ọ ni ajara ọlọla, irugbin rere patapata: ẽṣe ti iwọ fi yipada di ẹka ajara ajeji si mi? 22 Nitori iwọ iba wẹ ara rẹ ni ẽru, ki o si mu ọṣẹ pupọ, ẽri ni ẹ̀ṣẹ rẹ niwaju mi sibẹsibẹ, li Oluwa Ọlọrun wi. 23 Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka. 24 Kẹtẹkẹtẹ igbẹ ti ima gbe aginju, ninu ifẹ ọkàn rẹ̀ ti nfa ẹfufu, li akoko rẹ̀, tani le yi i pada? gbogbo awọn ti nwá a kiri kì yio da ara wọn li agara, nwọn o ri i li oṣu rẹ̀. 25 Da ẹsẹ̀ rẹ duro ni aiwọ bàta, ati ọfun rẹ ninu ongbẹ: ṣugbọn iwọ wipe, lasan ni! bẹ̃kọ, nitoriti emi ti fẹ awọn alejo, awọn li emi o tọ̀ lẹhin.

Ó Tọ́ kí Israẹli Jìyà

26 Gẹgẹ bi oju ti itì ole nigbati a ba mu u, bẹ̃li oju tì ile Israeli; awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn pẹlu. 27 Ti nwọn wi fun igi pe, Iwọ ni baba mi; ati fun okuta pe, iwọ li o bi mi. Nitori nwọn ti yi ẹ̀hìn wọn pada si mi kì iṣe iwaju wọn: ṣugbọn ni igba ipọnju wọn, nwọn o wipe, Dide, ki o gbani. 28 Njẹ nibo li awọn ọlọrun rẹ wà, ti iwọ ti da fun ara rẹ? jẹ ki nwọn ki o dide, bi nwọn ba le gba ọ nigba ipọnju rẹ, nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃li ọlọrun rẹ, iwọ Juda. 29 Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi. 30 Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun. 31 Iran enia yi, ẹ kiyesi ọ̀rọ Oluwa. Emi ha ti di aginju si Israeli bi? tabi ilẹ okunkun biribiri, ẽṣe ti enia mi wipe, awa nrin kakiri, awa kì yio tọ̀ ọ wá mọ. 32 Wundia le gbagbe ohun ọṣọ rẹ̀, tabi iyawo ọjá-ọṣọ rẹ̀? ṣugbọn enia mi ti gbagbe mi li ọjọ ti kò ni iye. 33 Ẽṣe ti iwọ tun ọ̀na rẹ ṣe lati wá ifẹ rẹ? nitorina iwọ ṣe kọ́ awọn obinrin buburu li ọ̀na rẹ. 34 Pẹlupẹlu ẹjẹ ẹmi awọn talaka ati alaiṣẹ mbẹ lara aṣọ rẹ, iwọ kò ri wọn nibi irunlẹ wọle, ṣugbọn lara gbogbo wọnyi. 35 Sibẹ iwọ wipe, alaiṣẹ̀ li emi, ibinu rẹ̀ yio sa yipada lọdọ mi. Sa wò o, emi o ba ọ jà, nitori iwọ wipe, emi kò ṣẹ̀. 36 Ẽṣe ti iwọ ṣe ati yi ọ̀na rẹ pada bẹ̃, oju yio tì ọ pẹlu fun Egipti, gẹgẹ bi oju ti tì ọ fun Assiria. 37 Lõtọ iwọ o kuro lọdọ rẹ̀, iwọ o si ka ọwọ le ori, nitori Oluwa ti kọ̀ awọn onigbẹkẹle rẹ, iwọ kì yio si ṣe rere ninu wọn.

Jeremiah 3

Israẹli Alaiṣododo

1 SA wò o, bi a wipe ọkunrin kan kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti aya na si kuro lọdọ rẹ̀, ti o si di aya ẹlomiran, ọkunrin na le tun tọ̀ ọ wá? ilẹ na kì yio di ibajẹ gidigidi? ṣugbọn iwọ ti ba ayanfẹ pupọ ṣe panṣaga, iwọ o tun tọ̀ mi wá! li Oluwa wi. 2 Gbe oju rẹ soke si ibi giga wọnnì, ki o si wò, nibo ni a kò ti bà ọ jẹ? Iwọ joko de wọn li oju ọ̀na, bi ara Arabia kan ni iju, iwọ si ti fi agbere ati ìwa buburu rẹ bà ilẹ na jẹ. 3 Nitorina emi fa ọ̀wara òjo sẹhin, kò si òjo arọkuro, sibẹ iwọ ni iwaju agbere, iwọ kọ̀ lati tiju. 4 Lõtọ lati isisiyi, iwọ kì yio ha pè mi pe, Baba mi! iwọ li ayanfẹ ìgba-ewe mi? 5 On o ha pa ibinu rẹ̀ mọ lailai? yio pa a mọ de opin? sa wò o, bayi ni iwọ ti wi, ṣugbọn iwọ ṣe ohun buburu li aidẹkun.

Israẹli ati Juda Gbọdọ̀ Ronu piwa da

6 Oluwa si wi fun mi ni igba Josiah ọba, pe, Iwọ ri ohun ti Israeli apẹhinda ti ṣe? o ti gun ori oke giga gbogbo, ati labẹ gbogbo igi tutu, nibẹ li o ti ṣe panṣaga. 7 Emi si wipe, lẹhin ti o ti ṣe gbogbo ohun wọnyi tan, yio yipada si mi, ṣugbọn kò yipada, Juda alarekereke arabinrin rẹ̀ si ri i. 8 Emi si wò pe, nitori gbogbo wọnyi ti Israeli apẹhinda ti ṣe agbere, ti mo kọ̀ ọ silẹ ti emi si fun u ni iwe-ikọsilẹ, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò bẹ̀ru, o si nṣe agbere lọ pẹlu. 9 O si ṣe nitori okìki àgbere rẹ̀ li o fi bà ilẹ jẹ, ti o si ṣe àgbere tọ̀ okuta ati igi lọ. 10 Lẹhin gbogbo wọnyi, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò yipada si mi tọkàntọkàn ṣugbọn li agabagebe; li Oluwa wi. 11 Oluwa si wi fun mi pe, Israeli apẹhinda, ti dá ara rẹ̀ li are ju Juda alarekereke lọ. 12 Lọ ki o si kede ọ̀rọ wọnyi ni iha ariwa, ki o si wipe, Yipada iwọ Israeli, apẹhinda, li Oluwa wi, emi kì yio jẹ ki oju mi ki o korò si ọ; nitori emi ni ãnu, li Oluwa wi, emi kì o si pa ibinu mi mọ titi lai. 13 Sa jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ pe, iwọ ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe, o si tú ọ̀na rẹ ka fun awọn alejo labẹ igi tutu gbogbo, ṣugbọn ẹnyin kò gba ohùn mi gbọ́, li Oluwa wi. 14 Pada, ẹnyin apẹhinda ọmọ, li Oluwa wi, nitori emi gbe nyin ni iyawo; emi o si mu nyin, ọkan ninu ilu kan, ati meji ninu idile kan; emi o si mu nyin wá si Sioni. 15 Emi o si fun nyin li oluṣọ-agutan gẹgẹ bi ti inu mi, ti yio fi ìmọ ati oye bọ́ nyin. 16 Yio si ṣe nigbati ẹnyin ba pọ̀ si i, ti ẹ si dàgba ni ilẹ na, li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi; nwọn kì yio si tun le wipe, Apoti-ẹri majẹmu Oluwa; bẹ̃ni kì yio wọ inu wọn, nwọn kì yio si ranti rẹ̀, nwọn kì yio tọ̀ ọ wá pẹlu, bẹ̃ni a kì yio si tun ṣe e mọ. 17 Nigbana ni nwọn o pè Jerusalemu ni itẹ Oluwa; gbogbo orilẹ-ède yio kọja tọ̀ ọ wá si orukọ Oluwa, si Jerusalemu, bẹ̃ni nwọn kì yio rìn mọ nipa agidi ọkàn buburu wọn, 18 Li ọjọ wọnnì, ile Juda yio rin pẹlu ile Israeli, nwọn o jumọ wá lati ilẹ ariwa, si ilẹ ti emi ti fi fun awọn baba nyin li ogún.

Ìbọ̀rìṣà Àwọn Eniyan Ọlọrun

19 Emi si wipe, Bawo li emi o ṣe gbe ọ kalẹ pẹlu awọn ọmọ, ati lati fun ọ ni ilẹ ayanfẹ, ogún daradara, ani ogún awọn orilẹ-ède? Emi si wipe, Iwọ o pè mi ni, Baba mi! iwọ kì o si pada kuro lọdọ mi. 20 Nitõtọ gẹgẹ bi aya ti ifi arekereke lọ kuro lọdọ ọkọ rẹ̀, bẹ̃ni ẹnyin ti hùwa arekereke si mi, iwọ ile Israeli: li Oluwa wi. 21 A gbọ́ ohùn kan lori ibi giga, ẹkun, ani ẹ̀bẹ awọn ọmọ Israeli pe: nwọn ti bà ọ̀na wọn jẹ, nwọn si ti gbagbe Oluwa, Ọlọrun wọn. 22 Yipada, ẹnyin ọmọ apẹhinda, emi o si wò ipẹhinda nyin sàn; Sa wò o, awa tọ̀ ọ wá, nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun wa! 23 Lotitọ asan ni eyi ti o ti oke wá, ani ọ̀pọlọpọ oke giga, lõtọ ninu Oluwa Ọlọrun wa ni igbala Israeli wà. 24 Ṣugbọn ohun itiju oriṣa ti jẹ ère iṣẹ awọn baba wa lati igba ewe wa wá, ọwọ́-ẹran wọn ati agbo-ẹran wọn, pẹlu ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn. 25 Awa dubulẹ ninu itiju wa, rudurudu wa bò wa mọlẹ, nitoriti awa ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun wa, awa pẹlu awọn baba wa, lati igba ewe wa wá, titi di oni yi, awa kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.

Jeremiah 4

Ìpè sí Ìrònúpìwàdà

1 Israeli bi iwọ o ba yipada, li Oluwa wi, yipada sọdọ mi; ati bi iwọ o ba mu irira rẹ kuro niwaju mi, iwọ kì o si rìn kiri: 2 Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀. 3 Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ọkunrin Juda, ati Jerusalemu pe, tú ilẹ titun fun ara nyin, ki ẹ má si gbìn lãrin ẹ̀gun. 4 Ẹ kọ ara nyin ni ilà fun Oluwa, ki ẹ si mu awọ ikọla ọkàn nyin kuro, ẹnyin enia Juda ati olugbe Jerusalemu, ki ikannu mi ki o má ba jade bi iná, ki o si jo tobẹ̃ ti kò si ẹniti o le pa a, nitori buburu iṣe nyin.

A fi Ogun Halẹ̀ mọ́ Juda

5 Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì. 6 Ẹ gbé ọpagun soke siha Sioni; ẹ kuro, ẹ má duro: nitori emi o mu buburu lati ariwa wá pẹlu ibajẹ nlanla. 7 Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe. 8 Nitori eyi, di amure aṣọ ọ̀fọ, pohùnrere ki o si sọkun: nitori ibinu gbigbona Oluwa kò lọ kuro lọdọ wa. 9 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ọkàn ọba yio nù, ati ọkàn awọn ijoye: awọn alufa yio si dãmu, hà yio si ṣe awọn woli. 10 Nigbana ni mo wipe, Ye! Oluwa Ọlọrun! nitõtọ iwọ ti tan awọn enia yi ati Jerusalemu jẹ gidigidi, wipe, Ẹnyin o ni alafia; nigbati idà wọ inu ọkàn lọ. 11 Nigbana ni a o wi fun awọn enia yi ati fun Jerusalemu pe, Ẹfũfu gbigbona lati ibi giga ni iju niha ọmọbinrin enia mi, kì iṣe lati fẹ, tabi lati fẹnù. 12 Ẹfũfu ti o lagbara jù wọnyi lọ yio fẹ fun mi: nisisiyi emi pẹlu yio sọ̀rọ idajọ si wọn.

Àwọn Ọ̀tá yí Juda Ká

13 Sa wò o, on o dide bi awọsanma, kẹ̀kẹ rẹ̀ yio dabi ìji: ẹṣin rẹ̀ yara jù idì lọ. Egbe ni fun wa! nitori awa di ijẹ. 14 Jerusalemu! wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ là. Yio ti pẹ to ti iro asan yio wọ̀ si inu rẹ. 15 Nitori ohùn kan kede lati Dani wá, o si pokiki ipọnju lati oke Efraimu. 16 Ẹ wi fun awọn orilẹ-ède; sa wò o, kede si Jerusalemu, pe, awọn ọluṣọ-ogun ti ilẹ jijin wá, nwọn si sọ ohùn wọn jade si ilu Juda. 17 Bi awọn ti nṣọ oko, bẹ̃ni nwọn wà yi i kakiri: nitori o ti ṣọtẹ̀ si mi, li Oluwa wi. 18 Ìwa rẹ ati iṣe rẹ li o ti mu gbogbo ohun wọnyi bá ọ; eyi ni buburu rẹ, nitoriti o korò, nitoriti o de ọkàn rẹ.

Ìbànújẹ́ Jeremiah nítorí Àwọn Eniyan Rẹ̀

19 Inu mi, inu mi! ẹ̀dun dùn mi jalẹ de ọkàn mi; ọkàn mi npariwo ninu mi; emi kò le dakẹ, Nitoriti iwọ, ọkàn mi, ngbọ́ iro fère, ati idagiri ogun. 20 Iparun lori iparun ni a nke; nitori gbogbo ilẹ li o ti parun, lojiji ni agọ mi di ijẹ, pẹlu aṣọ ikele mi ni iṣẹju kan. 21 Yio ti pẹ to ti emi o ri ọpagun, ti emi o si gbọ́ iro fère? 22 Nitori òpe li enia mi, nwọn kò mọ̀ mi; alaimoye ọmọ ni nwọn iṣe, nwọn kò si ni ìmọ: nwọn ni ọgbọ́n lati ṣe ibi, ṣugbọn oye ati ṣe rere ni nwọn kò ni.

Ìran tí Jeremiah Rí nípa Ìparun Tí Ń Bọ̀

23 Mo bojuwo aiye, sa wò o, o wà ni jũju, o si ṣofo; ati ọrun, imọlẹ kò si lara rẹ̀. 24 Mo bojuwo gbogbo oke nla, sa wò o, o warìri ati gbogbo oke kekere mì jẹjẹ. 25 Mo bojuwo, sa wò o, kò si enia kan, pẹlupẹlu gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun sa lọ. 26 Mo bojuwo, sa wò o, Karmeli di aginju, ati gbogbo ilu rẹ̀ li o wó lulẹ, niwaju Oluwa ati niwaju ibinu rẹ̀ gbigbona. 27 Nitori bayi li Oluwa wi pe: Gbogbo ilẹ ni yio di ahoro; ṣugbọn emi kì yio ṣe ipari tan. 28 Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀. 29 Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn. 30 Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ. 31 Nitori mo ti gbọ́ ohùn kan bi ti obinrin ti nrọbi, irora bi obinrin ti nbi akọbi ọmọ rẹ̀, ohùn ọmọbinrin Sioni ti npohùnrere ẹkun ara rẹ̀, ti o nnà ọwọ rẹ̀ wipe: Egbé ni fun mi nisisiyi nitori ãrẹ mu mi li ọkàn, nitori awọn apania.

Jeremiah 5

1 Ẹrìn kiri la ita Jerusalemu ja, ki ẹ si wò nisisiyi, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si wakiri nibi gbigbòro rẹ̀, bi ẹ ba lè ri ẹnikan, bi ẹnikan wà ti nṣe idajọ, ti o nwá otitọ; emi o si dari ji i. 2 Bi nwọn ba si wipe, Oluwa mbẹ; sibẹ nwọn bura eke. 3 Oluwa, oju rẹ kò ha wà lara otitọ? iwọ ti lù wọn, ṣugbọn kò dùn wọn; iwọ ti run wọn, ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gba ẹkọ: nwọn ti mu oju wọn le jù apata lọ; nwọn kọ̀ lati yipada. 4 Emi si wipe, Lõtọ talaka enia ni awọn wọnyi, nwọn kò ni oye, nitori nwọn kò mọ̀ ọ̀na Oluwa, tabi idajọ Ọlọrun wọn. 5 Emi o tọ̀ awọn ẹni-nla lọ, emi o si ba wọn sọrọ; nitori nwọn ti mọ̀ ọ̀na Oluwa, idajọ Ọlọrun wọn. Ṣugbọn awọn wọnyi ti jumọ ṣẹ́ àjaga, nwọn si ti ja ìde. 6 Nitorina kiniun lati inu igbo wa yio pa wọn, ikõko aṣálẹ̀ yio pa wọn run, ẹkùn yio mã ṣọ ilu wọn: ẹnikẹni ti o ba ti ibẹ jade li a o ya pẹrẹpẹrẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wọn pọ̀, ati ipẹhinda wọn le. 7 Emi o ha ṣe dari eyi ji ọ? awọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si fi eyi ti kì iṣe ọlọrun bura: emi ti mu wọn bura, ṣugbọn nwọn ṣe panṣaga, nwọn si kó ara wọn jọ si ile àgbere. 8 Nwọn jẹ akọ ẹṣin ti a bọ́ rere ti nrin kiri, olukuluku nwọn nyán si aya aladugbo rẹ̀. 9 Emi kì yio ha ṣe ibẹwo nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lara iru orilẹ-ède bi eyi? 10 Ẹ goke lọ si ori odi rẹ̀, ki ẹ si parun; ṣugbọn ẹ máṣe pa a run tan: ẹ wó kùrùkúrù rẹ̀ kuro nitori nwọn kì iṣe ti Oluwa. 11 Nitori ile Israeli ati ile Juda ti huwa arekereke gidigidi si mi, li Oluwa wi.

Ọlọrun kọ Israẹli sílẹ̀

12 Nwọn sẹ Oluwa, wipe, Kì iṣe on, ibi kò ni wá si ori wa, awa kì yio si ri idà tabi ìyan: 13 Awọn woli yio di ẹfufu, ọ̀rọ kò sì si ninu wọn: bayi li a o ṣe si wọn. 14 Nitorina bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, nitori ẹnyin sọ ọ̀rọ yi, sa wò o, emi o sọ ọ̀rọ mi li ẹnu rẹ di iná, ati awọn enia yi di igi, yio si jo wọn run. 15 Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi. 16 Apó ọfa rẹ̀ dabi isa-okú ti a ṣi, akọni enia ni gbogbo wọn. 17 On o si jẹ ikore rẹ ati onjẹ rẹ, nwọn o jẹ awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin rẹ, nwọn o si jẹ agbo rẹ ati ọwọ́-ẹran rẹ, nwọn o jẹ àjara rẹ ati igi ọ̀pọtọ rẹ, nwọn o fi idà sọ ilu olodi rẹ ti iwọ gbẹkẹle di ahoro. 18 Ṣugbọn li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi, emi kì yio ṣe iparun nyin patapata. 19 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin o wipe: Ẽṣe ti Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo ohun wọnyi si wa? nigbana ni iwọ o da wọn lohùn: Gẹgẹ bi ẹnyin ti kọ̀ mi, ti ẹnyin si nsìn ọlọrun ajeji ni ilẹ nyin, bẹ̃ni ẹnyin o sin alejo ni ilẹ ti kì iṣe ti nyin.

Ọlọrun Kìlọ̀ fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

20 Kede eyi ni ile Jakobu, pokiki rẹ̀ ni Juda wipe, 21 Ẹ gbọ́ eyi nisisiyi, ẹnyin aṣiwere enia ati alailọgbọ́n; ti o ni oju, ti kò si riran, ti o ni eti ti kò si gbọ́. 22 Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja? 23 Ṣugbọn enia yi ni aiya isàgun ati iṣọtẹ si, nwọn sọ̀tẹ, nwọn si lọ. 24 Bẹ̃ni nwọn kò wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa wayi, ẹniti o fun wa ni òjo akọrọ ati arọkuro ni igba rẹ̀: ti o fi ọ̀sẹ ikore ti a pinnu pamọ fun wa. 25 Aiṣedede nyin ti yi gbogbo ohun wọnyi pada, ati ẹ̀ṣẹ nyin ti fà ohun rere sẹhin kuro lọdọ nyin. 26 Nitori lãrin enia mi ni a ri enia ìka, nwọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okùn nwọn mu enia. 27 Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀. 28 Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka. 29 Emi kì yio ha ṣe ibẹwò nitori nkan wọnyi, li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lori orilẹ-ède bi eyi? 30 Ohun iyanu ati irira li a ṣe ni ilẹ na. 31 Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?

Jeremiah 6

Àwọn Ọ̀tá Yí Jerusalẹmu Ká

1 ẸNYIN ọmọ Benjamini, ẹ ko ẹrù nyin salọ kuro li arin Jerusalemu, ẹ si fun fère ni Tekoa, ki ẹ si gbe àmi soke ni Bet-hakeremu, nitori ibi farahàn lati ariwa wá; ani iparun nlanla. 2 Emi ti pa ọmọbinrin Sioni run, ti o ṣe ẹlẹgẹ ati ẹlẹwà. 3 Awọn oluṣọ-agutan pẹlu agbo wọn yio tọ̀ ọ wá, nwọn o pa agọ wọn yi i ka olukuluku yio ma jẹ ni àgbegbe rẹ̀. 4 Ẹ ya ara nyin si mimọ́ lati ba a jagun; dide, ki ẹ si jẹ ki a goke li ọsan. Egbe ni fun wa! nitori ọjọ nlọ, nitori ojiji ọjọ alẹ nà jade. 5 Dide, ẹ jẹ ki a goke lọ li oru, ki a si pa ãfin rẹ̀ run. 6 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ke igi lulẹ, ki ẹ si wà yàra ka Jerusalemu; eyi ni ilu nla ti a o bẹ̀wo; kìki ininilara li o wà lãrin rẹ̀. 7 Bi isun ti itú omi rẹ̀ jade, bẹ̃ni o ntú ìwa-buburu rẹ̀ jade: ìwa-ipa ati ìka li a gbọ́ niwaju mi nigbagbogbo ninu rẹ̀, ani aisan ati ọgbẹ́. 8 Gbọ́ ẹkọ́, Jerusalemu, ki ẹmi mi ki o má ba lọ kuro lọdọ rẹ; ki emi má ba sọ ọ di ahoro, ilẹ ti a kò gbe inu rẹ̀.

Israẹli Ọlọ̀tẹ̀

9 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, jẹ ki nwọn ki o pẽṣẹ iyokù Israeli bi àjara: yi ọwọ rẹ pada bi aká-eso-ajara sinu agbọ̀n. 10 Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀. 11 Nitorina emi kún fun ikannu Oluwa, ãrẹ̀ mu mi lati pa a mọra: tu u jade sori ọmọde ni ita, ati sori ajọ awọn ọmọkunrin pẹlu: nitori a o mu bãle pẹlu aya rẹ̀ ni igbekun, arugbo pẹlu ẹniti o ni ọjọ kikún lori. 12 Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi. 13 Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke. 14 Nwọn si ti wo ọgbẹ ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀; nwọn wipe, Alafia! Alafia! nigbati kò si alafia. 15 A mu itiju ba wọn, nitoriti nwọn ṣe ohun irira: sibẹ nwọn kò tiju kan pẹlu, pẹlupẹlu õru itiju kò mu wọn: nitorina nwọn o ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu: nigbati emi ba bẹ̀ wọn wo, a o wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.

Israẹli Kọ Ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀

16 Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin. 17 Pẹlupẹlu mo fi oluṣọ sọdọ nyin, ti o wipe, Ẹ fi eti si iro fère. Ṣugbọn nwọn wipe, awa kì yio feti si i. 18 Nitorina, gbọ́, ẹnyin orilẹ-ède, ki ẹ si mọ̀, ẹnyin ijọ enia, ohun ti o wà ninu wọn! 19 Gbọ́, iwọ ilẹ! wò o, emi o mu ibi wá si ori enia yi, ani eso iro inu wọn, nitori nwọn kò fi eti si ọ̀rọ mi, ati ofin mi ni nwọn kọ̀ silẹ. 20 Ère wo li o wà fun mi ninu turari lati Ṣeba wá, ati ẽsu daradara lati ilẹ ti o jina wá? ọrẹ sisun nyin kò ṣe inu-didun mi, ẹbọ jijẹ nyin kò wù mi. 21 Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ohun idugbolu siwaju awọn enia yi, ti baba ati awọn ọmọ yio jumọ ṣubu lù wọn, aladugbo ati ọrẹ rẹ̀ yio ṣegbe.

Ogun láti Ìhà Àríwá

22 Bayi li Oluwa wi, sa wò o, enia kan ti ilu ariwa wá, ati orilẹ-ède nla kan yio ti opin ilẹ aiye dide wá. 23 Nwọn di ọrun ati ọ̀kọ mu; onroro ni nwọn, nwọn kò ni ãnu; ohùn wọn yio hó bi okun; nwọn gun ẹṣin; nwọn si mura bi ọkunrin ti yio ja ọ logun, iwọ ọmọbinrin Sioni. 24 Awa ti gbọ́ òkiki eyi na: ọwọ wa di rirọ, ẹ̀dun ti di wa mu, ati irora bi obinrin ti nrọbi. 25 Máṣe lọ si inu oko, bẹ̃ni ki o má si rin oju ọ̀na na, nitori idà ọ̀ta, idagiri wà yikakiri. 26 Iwọ, ọmọbinrin enia mi, di ara rẹ ni amure aṣọ-ọ̀fọ ki o si ku ẽru sara, ṣe ọ̀fọ bi ẹniti nṣọ̀fọ fun ọmọ rẹ̀ nikanṣoṣo, pohùnrere kikoro: nitori afiniṣe-ijẹ yio ṣubu lù wa lojiji. 27 Emi ti fi ọ ṣe ẹniti o ma dán ni wò, odi alagbara lãrin enia mi, ki iwọ ki o le mọ̀ ki o si le dan ọ̀na wọn wò. 28 Gbogbo nwọn ni alagidi ọlọtẹ̀, ti nrin kiri sọ̀rọ̀ ẹni lẹhin, idẹ ati irin ni nwọn; abanijẹ ni gbogbo nwọn iṣe. 29 Ẹwìri joná, iná ti jẹ ojé, ẹniti nyọ ọ, nyọ ọ lasan, a kò si ya enia buburu kuro. 30 Fàdaka bibajẹ ni enia yio ma pè wọn, nitori Oluwa ti kọ̀ wọn silẹ.

Jeremiah 7

Jeremiah Waasu ninu Tẹmpili

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá wipe: 2 Duro ni ẹnu ilẹkun ile Oluwa, ki o si kede ọ̀rọ yi wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin ti Juda ti ẹ wọ̀ ẹnu ilẹkun wọnyi lati sin Oluwa. 3 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe, emi o si jẹ ki ẹnyin ma gbe ibi yi. 4 Ẹ máṣe gbẹkẹle ọ̀rọ eke, wipe: Tempili Oluwa, Tempili Oluwa, Tempili Oluwa ni eyi! 5 Nitori bi ẹnyin ba tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe nitõtọ; ti ẹnyin ba ṣe idajọ otitọ jalẹ, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀. 6 Ti ẹnyin kò ba si ṣẹ́ alejo ni iṣẹ́, alainibaba ati opó, ti ẹnyin kò si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ni ibi yi, ti ẹnyin kò si rìn tọ ọlọrun miran si ipalara nyin. 7 Nigbana ni emi o mu nyin gbe ibi yi, ni ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin lai ati lailai. 8 Sa wò o, ẹnyin gbẹkẹle ọ̀rọ eke, ti kò ni ère. 9 Kohaṣepe, ẹnyin njale, ẹ npania, ẹ nṣe panṣaga, ẹ nbura eke, ẹ nsun turari fun Baali, ẹ si nrin tọ ọlọrun miran ti ẹnyin kò mọ̀? 10 Ẹnyin si wá, ẹ si duro niwaju mi ni ile yi, ti a fi orukọ mi pè! ẹnyin si wipe: Gbà wa, lati ṣe gbogbo irira wọnyi? 11 Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi. 12 Ẹ si lọ nisisiyi, si ibujoko mi, ti o wà ni Ṣilo, ni ibi ti emi fi orukọ mi si li àtetekọṣe, ki ẹ si ri ohun ti emi ṣe si i nitori ìwa-buburu enia mi, Israeli. 13 Njẹ nisisiyi, nitori ẹnyin ti ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi, li Oluwa wi, ti emi si ba nyin sọ̀rọ, ti emi ndide ni kutukutu ti mo si nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́; ti emi si npè nyin, ṣugbọn ẹnyin kò dahùn. 14 Nitorina li emi o ṣe si ile yi, ti a pè ni orukọ mi, ti ẹ gbẹkẹle, ati si ibi ti emi fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin, gẹgẹ bi emi ti ṣe si Ṣilo. 15 Emi o si ṣá nyin tì kuro niwaju mi, gẹgẹ bi mo ti ṣá awọn arakunrin nyin tì, ani gbogbo iru-ọmọ Efraimu.

Àìgbọràn Àwọn Eniyan Náà

16 Nitorina máṣe gbadura fun enia yi, bẹ̃ni ki o má si gbe igbe rẹ soke ati adura fun wọn, bẹ̃ni ki o má ṣe rọ̀ mi: nitori emi kì yio gbọ́ tirẹ. 17 Iwọ kò ha ri ohun ti nwọn nṣe ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu? 18 Awọn ọmọ ko igi jọ, awọn baba nda iná, awọn obinrin npò akara lati ṣe akara didùn fun ayaba-ọrun ati lati tú ẹbọ-ọrẹ mimu jade fun ọlọrun miran, ki nwọn ki o le rú ibinu mi soke. 19 Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn? 20 Nitorina bayi li Ọlọrun Oluwa wi, sa wò o, a o dà ibinu ati irunu mi si ibi yi, sori enia ati sori ẹranko, ati sori igi igbo, ati sori eso ilẹ, yio si jo, a kì o le pa iná rẹ̀. 21 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, kó ẹbọ sisun nyin pẹlu ẹbọ jijẹ nyin, ki ẹ si jẹ ẹran. 22 Nitori emi kò wi fun awọn baba nyin, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn ni ọjọ ti mo mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti niti ẹbọ sisun tabi ẹbọ jijẹ: 23 Ṣugbọn eyi ni mo paṣẹ fun wọn wipe, Gba ohùn mi gbọ́, emi o si jẹ Ọlọrun nyin, ẹnyin o si jẹ enia mi: ki ẹ si rin ni gbogbo ọ̀na ti mo ti paṣẹ fun nyin, ki o le dara fun nyin. 24 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹ eti silẹ, nwọn si rin ni ìmọ ati agidi ọkàn buburu wọn, nwọn si kọ̀ ẹ̀hin wọn kì iṣe oju wọn si mi. 25 Lati ọjọ ti baba nyin ti ilẹ Egipti jade wá titi di oni, emi ti rán gbogbo iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, lojojumọ emi dide ni kutukutu, emi si rán wọn. 26 Sibẹ nwọn kò gbọ́ temi, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ, sugbọn nwọn mu ọrun le, nwọn ṣe buburu jù awọn baba wọn lọ. 27 Bi iwọ ba si wi gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, nwọn kì yio gbọ́ tirẹ: iwọ o si pè wọn, ṣugbọn nwọn kì o da ọ lohùn. 28 Iwọ o si wi fun wọn pe: Eyi ni enia na ti kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò gba ẹkọ́: otitọ ṣègbe, a si ke e kuro li ẹnu wọn.

Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀ ní Àfonífojì Hinomu

29 Fá irun ori rẹ, ki o si sọ ọ nù, ki o si sọkun lori oke: nitori Oluwa ti kọ̀ iran ibinu rẹ̀ silẹ, o si ṣa wọn tì. 30 Nitori awọn ọmọ Juda ti ṣe buburu niwaju mi, li Oluwa wi; nwọn ti gbe ohun irira wọn kalẹ sinu ile ti a pe li orukọ mi, lati ba a jẹ. 31 Nwọn si ti kọ́ ibi giga Tofeti, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati sun awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin wọn ninu iná; aṣẹ eyiti emi kò pa fun wọn, bẹ̃ni kò si wá si inu mi. 32 Nitorina sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti a kì o pe e ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn a o pe e ni afonifoji ipakupa: nitori nwọn o sin oku ni Tofeti, titi àye kì yio si mọ. 33 Okú awọn enia yi yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ: ẹnikan kì yio lé wọn kuro. 34 Emi o si mu ki ohùn inu-didun ki o da kuro ni ilu Juda ati kuro ni ita Jerusalemu, ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ iyawo, ati ti iyawo; nitori ilẹ na yio di ahoro.

Jeremiah 8

1 LI akoko na, li Oluwa wi, ni nwọn o hú egungun awọn ọba Juda ati egungun awọn ijoye, egungun awọn alufa ati egungun awọn woli, ati egungun awọn olugbe Jerusalemu kuro ninu isà wọn: 2 Nwọn o si tẹ́ wọn siwaju õrùn ati òṣupa ati gbogbo ogun ọrun, ti nwọn ti fẹ, ti nwọn si ti sìn, awọn ti nwọn si rìn tọ̀ lẹhin, ti nwọn si wá, ti nwọn si foribalẹ fun: a kì yio kó wọn jọ, bẹ̃li a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan li oju ilẹ-aiye. 3 Awon iyokù ti o kù ninu idile buburu yi yio yan kikú jù yiyè lọ: ni ibi gbogbo ti nwọn kù si, ti emi ti tì wọn jade si, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà

4 Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; enia le ṣubu li aidide mọ? tabi enia le pada, ki o má tun yipada mọ? 5 Ẽṣe ti awọn enia Jerusalemu yi sọ ipadasẹhin di ipẹhinda lailai? nwọn di ẹ̀tan mu ṣinṣin, nwọn kọ̀ lati pada. 6 Mo tẹti lélẹ, mo si gbọ́, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ titọ: kò si ẹnikan ti o ronupiwada buburu rẹ̀ wipe, kili emi ṣe? gbogbo nwọn yipo li ọ̀na wọn, bi akọ-ẹṣin ti nsare gburu sinu ogun. 7 Lõtọ ẹiyẹ àkọ li oju-ọrun mọ̀ akoko rẹ̀, àdaba ati ẹiyẹ lekeleke pẹlu alapandẹ̀dẹ sọ́ igba wiwá wọn; ṣugbọn enia mi kò mọ̀ idajọ Oluwa. 8 Bawo li ẹnyin ṣe wipe, Ọlọgbọ́n ni wa, ati ofin Oluwa mbẹ lọdọ wa? sa wò o nitõtọ! kalamu eke awọn akọwe ti sọ ofin di eke. 9 Oju tì awọn ọlọgbọ́n, idamu ba wọn a si mu wọn: sa wò o, nwọn ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa! ọgbọ́n wo li o wà ninu wọn? 10 Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan. 11 Nitoripe nwọn ti wo ipalara ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀ wipe, Alafia! Alafia! nigbati alafia kò si. 12 Itiju yio ba wọn nitori nwọn ti ṣe ohun irira, sibẹ nwọn kò tiju, bẹ̃ni õru itiju kò mu wọn, nitorina ni nwọn o ṣe ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu; ni igba ibẹ̀wo wọn, a o si wó wọn lulẹ, li Oluwa wi. 13 Ni kiká emi o ká wọn jọ, li Oluwa wi, eso-àjara kì yio si mọ lori ajara, tabi eso-ọ̀pọtọ lori igi ọ̀pọtọ, ewe rẹ̀ yio si rẹ̀; nitorina ni emi o yàn awọn ti yio kọja lọ lori rẹ̀. 14 Ẽṣe ti awa joko jẹ? ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si jẹ ki a wọ̀ inu ilu olodi, ki a si dakẹ sibẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wa, ti mu wa dakẹ, o si fun wa ni omi orõro lati mu, nitori ti awa ṣẹ̀ si Oluwa. 15 Awa reti alafia, ṣugbọn kò si ireti kan, ati ìgba didá ara, si kiye si i, idamu! 16 Lati Dani ni a gbọ́ fifọn imu ẹṣin rẹ̀; gbogbo ilẹ warìri fun iro yiyan akọ-ẹṣin rẹ̀; nwọn si de, nwọn si jẹ ile run, ati eyi ti mbẹ ninu rẹ̀: ilu ati awọn ti ngbe inu rẹ̀, 17 Sa wò o, emi o ran ejo, ejo gunte si ãrin nyin, ti kì yio gbọ́ ituju, nwọn o si bu nyin jẹ, li Oluwa wi.

Jeremiah Káàánú fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

18 Emi iba le tù ara mi ninu, ninu ikãnu mi? ọkàn mi daku ninu mi! 19 Sa wò o, ohùn ẹkún ọmọbinrin enia mi, lati ilẹ jijina wá, Kò ha si Oluwa ni Sioni bi? ọba rẹ̀ kò ha si ninu rẹ̀? ẽṣe ti nwọn fi ere gbigbẹ ati ohun asan àjeji mu mi binu? 20 Ikore ti kọja, ẹ̀run ti pari, a kò si gba wa la! 21 Nitori ipalara ọmọbinrin enia mi li a ṣe pa mi lara; emi ṣọ̀fọ, iyanu si di mi mu. 22 Kò ha si ojiya ikunra ni Gileadi, oniṣegun kò ha si nibẹ? ẽṣe ti a kò fi ọ̀ja dì ọgbẹ́ ọmọbinrin enia mi.

Jeremiah 9

1 ORI mi iba jẹ omi, ati oju mi iba jẹ orisun omije, ki emi le sọkun lọsan ati loru fun awọn ti a pa ninu ọmọbinrin enia mi! 2 A! emi iba ni buka ero ni iju, ki emi ki o le fi enia mi silẹ, ki nlọ kuro lọdọ wọn! nitori gbogbo nwọn ni panṣaga, ajọ alarekereke enia ni nwọn. 3 Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi. 4 Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin. 5 Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede. 6 Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi. 7 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi. 8 Ahọn wọn dabi ọfa ti a ta, o nsọ ẹ̀tan, ẹnikini nfi ẹnu rẹ̀ sọ alafia fun ẹnikeji rẹ̀, ṣugbọn li ọkàn rẹ̀ o ba dè e. 9 Emi kì yio ha bẹ̀ wọn wò nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ọkàn mi kì yio ha gbẹsan lara orilẹ-ède bi iru eyi? 10 Fun awọn oke-nla ni emi o gbe ẹkún ati ohùnrere soke, ati ẹkún irora lori papa oko aginju wọnnì, nitoriti nwọn jona, ẹnikan kò le kọja nibẹ, bẹ̃ni a kò gbọ́ ohùn ẹran-ọsin, lati ẹiyẹ oju-ọrun titi de ẹranko ti sa kuro, nwọn ti lọ. 11 Emi o sọ Jerusalemu di okiti àlapa, ati iho awọn ikõko, emi o si sọ ilu Juda di ahoro, laini olugbe. 12 Tani enia na ti o gbọ́n, ti o moye yi? ati tani ẹniti ẹnu Oluwa ti sọ fun, ki o ba le kede rẹ̀, pe: kili o ṣe ti ilẹ fi ṣegbe, ti o si sun jona bi aginju, ti ẹnikan kò kọja nibẹ? 13 Oluwa si wipe, nitoriti nwọn ti kọ̀ ofin mi silẹ ti mo ti gbe kalẹ niwaju wọn, ti nwọn kò si gbà ohùn mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò si rin ninu rẹ̀. 14 Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn: 15 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro. 16 Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn.

Àwọn Eniyan Jerusalẹmu kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́

17 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá. 18 Ki nwọn ki o si yara, ki nwọn pohùnrere ẹkun fun wa, ki oju wa ki o le sun omije ẹkun, ati ki ipenpeju wa le tu omi jade. 19 Nitori a gbọ́ ohùn ẹkun lati Sioni, pe, A ti pa wa run to! awa dãmu jọjọ, nitoriti a kọ̀ ilẹ yi silẹ, nitoriti ibugbe wa tì wa jade. 20 Njẹ ẹnyin obinrin, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹ jẹ ki eti nyin gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀, ki ẹ si kọ́ ọmọbinrin nyin ni ẹkun, ati ki olukuluku obinrin ki o kọ́ aladugbo rẹ̀ ni arò. 21 Nitori iku ti de oju ferese wa, o ti wọ̀ inu ãfin wa, lati ke awọn ọmọ-ọmu kuro ni ita, ati awọn ọmọdekunrin kuro ni igboro. 22 Sọ pe, Bayi li Oluwa wi, Okú enia yio ṣubu bi àtan li oko, ati bi ibukunwọ lẹhin olukore, ti ẹnikan ko kojọ. 23 Bayi li Oluwa wi, ki ọlọgbọ́n ki o má ṣogo nitori ọgbọ́n rẹ̀, bẹ̃ni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọrọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀. 24 Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi. 25 Sa wò o, ọjọ mbọ̀ li Oluwa wi, ti emi o jẹ gbogbo awọn ti a kọ ni ilà pẹlu awọn alaikọla ni ìya; 26 Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.

Jeremiah 10

Ìbọ̀rìṣà ati Ìjọ́sìn Tòótọ́

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun nyin, ẹnyin ile Israeli: 2 Bayi li Oluwa wi, Ẹ máṣe kọ́ ìwa awọn keferi, ki àmi ọrun ki o má si dãmu nyin, nitoripe, nwọn ndamu awọn orilẹ-ède. 3 Nitori asan ni ilana awọn orilẹ-ède; nitori igi ti a ke lati igbo ni iṣẹ ọwọ oniṣọna ati ti ãke. 4 Nwọn fi fádaka ati wura ṣe e lọṣọ, nwọn fi iṣo ati olù dì i mu, ki o má le mì. 5 Nwọn nàro bi igi ọpẹ, ṣugbọn nwọn kò fọhùn: gbigbe li a ngbe wọn, nitori nwọn kò le rin. Má bẹ̀ru wọn; nitori nwọn kò le ṣe buburu, bẹ̃li ati ṣe rere, kò si ninu wọn. 6 Kò si ẹnikan ti o dabi Iwọ Oluwa! iwọ tobi, orukọ rẹ si tobi ni agbara! 7 Tani kì ba bẹ̀ru rẹ, Iwọ Ọba orilẹ-ède? nitori tirẹ ni o jasi; kò si ninu awọn ọlọgbọ́n orilẹ-ède, ati gbogbo ijọba wọn, kò si ẹniti o dabi Iwọ! 8 Ṣugbọn nwọn jumọ ṣe ope ati aṣiwere; ìti igi ni ẹkọ́ ohun asan. 9 Fadaka ti a fi ṣe awo ni a mu lati Tarṣiṣi wá, ati wura lati Upasi wá, iṣẹ oniṣọna, ati lọwọ alagbẹdẹ: alaro ati elese aluko ni aṣọ wọn: iṣẹ ọlọgbọ́n ni gbogbo wọn. 10 Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀. 11 Bayi li ẹnyin o wi fun wọn pe: Awọn ọlọrun ti kò da ọrun on aiye, awọn na ni yio ṣegbe loju aiye, ati labẹ ọrun wọnyi.

Orin Ìyìn sí Ọlọrun

12 On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀. 13 Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá. 14 Aṣiwere ni gbogbo enia nitori oye kò si: oju tì olukuluku alagbẹdẹ niwaju ere rẹ̀, nitori ère didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu rẹ̀. 15 Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: nigba ibẹwo wọn nwọn o ṣègbe. 16 Ipin Jakobu kò si dabi wọn nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo; Israeli si ni ẹya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. 17 Ko ẹrù rẹ kuro ni ilẹ na, Iwọ olugbe ilu ti a dotì. 18 Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o gbọ̀n awọn olugbe ilẹ na nù lẹ̃kan yi, emi o si pọ́n wọn loju, ki nwọn ki o le ri i. 19 Egbe ni fun mi nitori ipalara mi! ọgbẹ mi pọ̀: ṣugbọn mo wipe, nitõtọ ìya mi ni eyi, emi o si rù u. 20 Agọ mi bajẹ, gbogbo okùn mi si ja: awọn ọmọ mi ti fi mi silẹ lọ, nwọn kò sí mọ́, kò si ẹnikan ti yio nà agọ mi mọ, ti yio si ta aṣọ ikele mi. 21 Nitori awọn oluṣọ agutan ti di ope, nwọn kò si wá Oluwa: nitorina nwọn kì yio ri rere, gbogbo agbo wọn yio si tuka. 22 Sa wò o, ariwo igbe ti de, ati irukerudo nla lati ilẹ ariwa wá, lati sọ ilu Judah di ahoro, ati iho ọwawa. 23 Oluwa! emi mọ̀ pe, ọ̀na enia kò si ni ipa ara rẹ̀: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀. 24 Oluwa kilọ fun mi, ṣugbon ni idajọ ni, ki o máṣe ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má sọ mi di asan. 25 Tu ibinu rẹ si ori awọn orilẹ-ède, ti kò mọ̀ ọ, ati sori awọn idile ti kò ke pè orukọ rẹ, nitoriti nwọn ti jẹ Jakobu run, nwọn si gbe e mì, nwọn si pa a run tan, nwọn si sọ ibugbe rẹ̀ di ahoro.

Jeremiah 11

Jeremiah ati Majẹmu

1 Ọ̀RỌ ti o ti ọdọ Oluwa wá sọdọ Jeremiah wipe: 2 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi, ki ẹ si sọ fun awọn enia Juda ati awọn olugbe Jerusalemu, 3 Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Ifibu ni oluwarẹ̀ ti kò ba gbà ọ̀rọ majẹmu yi gbọ́, 4 Ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, li ọjọ ti mo mu wọn ti ilẹ Egipti jade, lati inu ileru irin wipe, Gbà ohùn mi gbọ́, ki ẹ si ṣe gẹgẹ bi emi ti paṣẹ fun nyin: bẹ̃ni ẹnyin o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin: 5 Ki emi ki o le mu ileri mi ṣẹ, ti mo ti bura fun awọn baba nyin, lati fun wọn ni ilẹ ti nṣàn fun wara ati fun oyin, gẹgẹ bi o ti ri li oni: mo si dahùn mo si wipe, Amin, Oluwa! 6 Oluwa si wi fun mi pe, Kede gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi ki ẹ si ṣe wọn. 7 Nitori ni kikilọ mo kilọ fun awọn baba nyin lati ọjọ ti mo ti mu wọn wá lati ilẹ Egipti, titi di oni, emi si nyara kilọ fun wọn, mo si nsọ wipe, Ẹ gbà ohùn mi gbọ́. 8 Sibẹsibẹ nwọn kò gbọ́, nwọn kò tẹti silẹ, nwọn si rìn, olukuluku wọn ni agidi ọkàn buburu wọn: nitorina emi o mu gbogbo ọ̀rọ majẹmu yi wá sori wọn, ti mo paṣẹ fun wọn lati ṣe; nwọn kò si ṣe e. 9 Oluwa si wi fun mi pe, A ri ìditẹ lãrin awọn ọkunrin Juda ati lãrin awọn olugbe Jerusalemu. 10 Nwọn yipada si ẹ̀ṣẹ iṣaju awọn baba wọn ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi; awọn wọnyi si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn: ile Israeli ati ile Juda ti dà majẹmu mi ti mo ba awọn baba wọn dá. 11 Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, Emi o mu ibi wá sori wọn, ti nwọn kì yio le yẹba fun: bi nwọn tilẹ ke pè mi, emi kì yio fetisi igbe wọn. 12 Jẹ ki ilu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu ki o lọ, ki nwọn ki o si ke pe awọn ọlọrun ti nwọn ńsun turari fun, ṣugbọn lõtọ nwọn kì yio le gba wọn ni igba ipọnju wọn. 13 Nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃ni iye ọlọrun rẹ, iwọ Juda, ati bi iye ita Jerusalemu, bẹ̃ni iye pẹpẹ ti ẹnyin ti tẹ́ fun ohun itìju nì, pẹpẹ lati sun turari fun Baali. 14 Nitorina máṣe gbadura fun awọn enia yi, bẹ̃ni ki o má si ṣe gbe ohùn ẹkun tabi ti adura soke fun wọn, nitori emi kì yio gbọ́ ni igba ti nwọn ba kigbe pè mi, ni wakati wahala wọn. 15 Kini olufẹ mi ni iṣe ni ile mi? nigbati nwọn nṣe buburu pupọ bayi? adura on ẹran mimọ́ ha le mu ibi kọja kuro lọdọ rẹ? bi o ba ri bayi? nigbana jẹ ki inu rẹ ki o dùn. 16 Oluwa pè orukọ rẹ ni igi Olifi tutu, didara, eleso rere: ṣugbọn nisisiyi o fi ariwo irọkẹkẹ nla dá iná lara rẹ̀, ẹka rẹ̀ li o si faya. 17 Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o gbìn ọ, ti sọ̀rọ ibi si ọ, nitori buburu ile Israeli, ati ile Juda, ti nwọn ti ṣe si ara wọn lati ru ibinu mi soke ni sisun turari fun Baali.

Ète láti Pa Jeremiah

18 Oluwa si ti mu mi mọ̀, emi si mọ̀: nigbana ni iwọ fi iṣe wọn hàn mi. 19 Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ. 20 Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun, onidajọ otitọ ti ndan aiya ati inu wò, emi o ri igbẹsan rẹ lori wọn: nitori iwọ ni mo fi ọ̀ran mi le lọwọ. 21 Nitorina bayi li Oluwa wi, niti enia Anatoti ti o nwá ẹmi rẹ, ti nwipe, Máṣe sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa, ki iwọ ki o má ba kú nipa, ọwọ wa. 22 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, wò o, emi o bẹ̀ wọn wo, awọn ọdọmọkunrin o ti ọwọ idà kú, ọmọ wọn ọkunrin ati ọmọ wọn obinrin yio kú nipa iyàn: 23 Ẹnikan kì yio kù ninu wọn: nitori emi o mu ibi wá sori awọn enia Anatoti, ani ọdun ìbẹwo wọn.

Jeremiah 12

1 ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu. 2 Iwọ ti gbìn wọn, nwọn si ti ta gbòngbo: nwọn dagba, nwọn si nso eso: iwọ sunmọ ẹnu wọn, o si jìna si ọkàn wọn. 3 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, mọ̀ mi: iwọ ri mi, o si dan ọkàn mi wò bi o ti ri si ọ: pa wọn mọ bi agutan fun pipa, ki o si yà wọn sọtọ fun ọjọ pipa. 4 Yio ti pẹ to ti ilẹ yio fi ma ṣọ̀fọ, ati ti ewe igbẹ gbogbo yio rẹ̀ nitori ìwa-buburu awọn ti mbẹ ninu rẹ̀? ẹranko ati ẹiyẹ nṣòfò nitori ti nwọn wipe, on kì o ri ẹ̀hin wa. 5 Bi iwọ ba ba ẹlẹsẹ rìn, ti ãrẹ si mu ọ, iwọ o ha ti ṣe ba ẹlẹṣin dije? ati pẹlu ni ilẹ alafia, bi iwọ ba ni igbẹkẹle, kini iwọ o ṣe ninu ẹkún odò Jordani? 6 Nitori pẹlupẹlu, awọn arakunrin rẹ, ati ile baba rẹ, awọn na ti hùwa ẹ̀tan si ọ, lõtọ, awọn na ti ho le ọ: Má gbẹkẹle wọn, bi nwọn tilẹ ba ọ sọ̀rọ daradara.

OLUWA Káàánú Àwọn Eniyan Rẹ̀

7 Emi ti kọ̀ ile mi silẹ, mo ti fi ogún mi silẹ; mo ti fi olufẹ ọ̀wọn ọkàn mi le ọta rẹ̀ lọwọ. 8 Ogún mi di kiniun ninu igbo fun mi; on kigbe soke si mi; nitorina ni mo ṣe korira rẹ̀. 9 Ogún mi di ẹranko ọ̀wawa fun mi, ẹranko yi i kakiri, ẹ lọ, ẹ ko gbogbo ẹran igbẹ jọ pọ̀, ẹ mu wọn wá jẹ. 10 Ọ̀pọlọpọ oluṣọ-agutan ba ọgba ajara mi jẹ, nwọn tẹ ipin oko mi mọlẹ labẹ ẹsẹ wọn, nwọn ti sọ ipin oko mi ti mo fẹ di aginju ahoro. 11 Nwọn ti sọ ọ di ahoro, o ṣọ̀fọ fun mi bi ahoro: gbogbo ilẹ ti di ahoro, nitori ti kò si ẹnikan ti o rò li ọkàn rẹ̀. 12 Awọn abanijẹ ti gori gbogbo ibi giga wọnni ni ọ̀dan, nitori idà Oluwa yio pa lati ikangun de ikangun ekeji ilẹ na, alafia kò si fun gbogbo alãye. 13 Nwọn ti gbin alikama, ṣugbọn nwọn o ka ẹ́gun, nwọn ti fi irora ẹ̀dun mu ara wọn, ṣugbọn nwọn kì yio ri anfani: ki oju ki o tì nyin nitori ère nyin, nitori ibinu gbigbona Oluwa.

Ìlérí OLUWA fún Àwọn Aládùúgbò Israẹli

14 Bayi li Oluwa wi si gbogbo awọn aladugbo buburu mi ti nwọn fi ọwọ kan ogún mi ti mo ti mu enia mi, Israeli, jogun. Sa wò o, emi o fa wọn tu kuro ni ilẹ wọn, emi o si fà ile Juda tu kuro larin wọn. 15 Yio si ṣe, nigba ti emi o ti fà wọn tu kuro tan, emi o pada, emi o si ni iyọ́nu si wọn, emi o si tun mu wọn wá, olukuluku wọn, si ogún rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀. 16 Yio si ṣe, bi nwọn ba ṣe ãpọn lati kọ́ ìwa enia mi, lati fi orukọ mi bura pe, Oluwa mbẹ: gẹgẹ bi nwọn ti kọ́ enia mi lati fi Baali bura; nigbana ni a o gbe wọn ró lãrin enia mi. 17 Ṣugbọn bi nwọn kì o gbọ́, emi o fà orilẹ-ède na tu patapata; emi o si pa wọn run, li Oluwa wi.

Jeremiah 13

Òwe Aṣọ Funfun

1 BAYI li Oluwa wi fun mi pe: Lọ, ki o si rà àmure aṣọ ọgbọ̀, ki o si dì i mọ ẹgbẹ rẹ, ki o má si fi i sinu omi. 2 Bẹ̃ li emi si rà àmure na, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, emi si dì i mọ ẹgbẹ mi. 3 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wa lẹ̃keji wipe: 4 Mu amure ti iwọ ti rà, ti o wà li ẹgbẹ rẹ, ki o si dide, lọ si odò Ferate, ki o si fi i pamọ nibẹ, ninu pàlapála okuta. 5 Bẹ̃ni mo lọ, emi si fi i pamọ leti odò Ferate, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun mi. 6 O si ṣe lẹhin ọjọ pupọ, Oluwa wi fun mi pe, Dide, lọ si odò Ferate, ki o si mu amure nì jade, ti mo paṣẹ fun ọ lati fi pamọ nibẹ. 7 Mo si lọ si odò Ferate, mo si walẹ̀, mo si mu àmure na jade kuro ni ibi ti emi ti fi i pamọ si, sa wò o, àmure na di hihù, kò si yẹ fun ohunkohun. 8 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe, 9 Bayi li Oluwa wi, Gẹgẹ bi eyi na ni emi o bà igberaga Juda jẹ, ati igberaga nla Jerusalemu. 10 Awọn enia buburu yi, ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi, ti nrin ni agidi ọkàn wọn, ti o si nrin tọ̀ awọn ọlọrun miran, lati sìn wọn ati lati foribalẹ fun wọn, yio si dabi àmure yi, ti kò yẹ fun ohunkohun. 11 Nitori bi amure iti lẹ̀ mọ ẹgbẹ enia, bẹ̃ni mo ṣe ki gbogbo ile Israeli ati gbogbo ile Juda ki o lẹ̀ mọ mi lara, li Oluwa wi, ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ati orukọ ati ogo, ati iyìn, ṣugbọn nwọn kò fẹ igbọ́.

Ìkòkò Waini

12 Nitorina ki iwọ ki o sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún: nwọn o si wi fun ọ pe, A kò ha mọ̀ nitõtọ pe, gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún? 13 Nigbana ni iwọ o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi imutipara kún gbogbo olugbe ilẹ yi, ani awọn ọba ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn alufa ati awọn woli, pẹlu gbogbo awọn olugbe Jerusalemu. 14 Emi o tì ekini lu ekeji, ani awọn baba ati awọn ọmọkunrin pọ̀, li Oluwa wi: emi kì yio dariji, bẹ̃ni emi kì o ṣãnu, emi kì yio ṣe iyọ́nu, lati má pa wọn run.

Jeremiah ṣe Ìkìlọ̀ nípa Ìgbéraga

15 Ẹ gbọ́, ki ẹ si fi eti silẹ; ẹ má ṣe gberaga: nitori ti Oluwa ti sọ̀rọ. 16 Ẹ fi ogo fun Oluwa Ọlọrun nyin, ki o to mu òkunkun wá, ati ki o to mu ẹsẹ nyin tase lori oke ṣiṣu wọnni, ati nigbati ẹnyin si nreti imọlẹ, on o sọ ọ di ojiji ikú, o si ṣe e bi òkunkun biribiri. 17 Ṣugbọn bi ẹnyin kì o gbọ́, ọkàn mi yio sọkun ni ibi ikọkọ, nitori igberaga na, oju mi yio sọkun kikan, yio sun omije pẹ̀rẹpẹ̀rẹ, nitori ti a kó agbo Oluwa lọ ni igbekun. 18 Sọ fun ọba ati fun ayaba pe, Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ, ẹ joko silẹ, nitori ade ogo nyin bọ́ si ilẹ lati ori nyin. 19 Ilu gusu wọnni ni a o si mọ, kò si ẹnikan ti yio ṣe wọn: a o kó Judah lọ ni igbekun gbogbo rẹ̀, a o kó wọn lọ patapata ni igbekun. 20 Gbe oju nyin soke, ki ẹ si wo awọn ti mbọ̀ lati ariwa! nibo ni agbo-ẹran nì wà, ti a ti fi fun ọ, agbo-ẹran rẹ daradara? 21 Kini iwọ o wi, nigbati on o fi awọn ti iwọ ti kọ́ lati ṣe korikosun rẹ jẹ olori lori rẹ, irora kì yio ha mu ọ bi obinrin ti nrọbi? 22 Bi iwọ ba si wi ninu ọkàn rẹ pe, Ẽṣe ti nkan wọnyi ṣe wá sori mi? Nitori ti ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ ni a ṣe ká aṣọ rẹ soke, ti a si fi agbara fi gigisẹ rẹ hàn ni ihoho. 23 Ara Etiopia le yi àwọ rẹ̀ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rẹ̀ pada? bẹ̃ni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ́ ni ìwa buburu? 24 Nitorina ni emi o tú wọn ka bi iyangbo ti nkọja lọ niwaju afẹfẹ aginju. 25 Eyi ni ipin rẹ, apakan òṣuwọn rẹ lọwọ mi, li Oluwa wi: nitori iwọ ti gbàgbe mi, ti o si gbẹkẹle eke. 26 Nitorina emi o ka aṣọ iṣẹti rẹ loju rẹ, ki itiju rẹ ki o le hàn sode. 27 Emi ti ri panṣaga rẹ, ati yiyan rẹ bi ẹṣin, buburu ìwa-agbere rẹ, ati ìwa irira rẹ lori oke ati ninu oko. Egbe ni fun ọ, iwọ Jerusalemu! iwọ kò le di mimọ́, yio ha ti pẹ to!

Jeremiah 14

Ọ̀gbẹlẹ̀ Ńlá

1 EYI li ọ̀rọ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah wá nipa ti ọdá. 2 Juda kãnu ati ẹnu-bode rẹ̀ wọnnì si jõro, nwọn dudu de ilẹ; igbe Jerusalemu si ti goke. 3 Awọn ọlọla wọn si ti rán awọn ọmọ wẹrẹ lọ si odò: nwọn wá si kanga, nwọn kò ri omi; nwọn pada pẹlu agbè wọn lofo, oju tì wọn, idãmu mu wọn, nwọn si bo ori wọn. 4 Nitori ilẹ, ti ndãmu gidigidi, nitoriti òjo kò si ni ilẹ, oju tì awọn àgbẹ, nwọn bo ori wọn. 5 Lõtọ abo-àgbọnrin pẹlu ni papa bimọ, o fi i silẹ nitori ti kò si koriko. 6 Ati awọn kẹtẹkẹtẹ-igbẹ duro lori oke wọnni, nwọn fọn imu si ẹfũfu bi ikõko, oju wọn rẹ̀ nitoriti kò si koriko. 7 Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀. 8 Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn? 9 Ẽṣe ti iwọ o dabi ẹniti o dãmu, bi ọkunrin akọni ti kò le ràn ni lọwọ? sibẹ iwọ, Oluwa, mbẹ li ãrin wa, a si npè orukọ rẹ mọ wa, má fi wa silẹ. 10 Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò. 11 Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere. 12 Nigbati nwọn ba gbãwẹ, emi kì yio gbọ́ ẹ̀bẹ wọn; nigbati nwọn ba ru ẹbọ-ọrẹ sisun ati ẹbọ-ọrẹ, inu mi kì o dùn si wọn: ṣugbọn emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-àrun pa wọn run. 13 Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi. 14 Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, awọn woli nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi; emi kò rán wọn, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn, emi kò si sọ̀rọ kan fun wọn, iran eke, afọṣẹ, ati ohun asan, ati ẹ̀tan inu wọn, ni awọn wọnyi sọtẹlẹ fun nyin. 15 Nitorina bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ li orukọ mi, ti emi kò rán; sibẹ nwọn wipe, Idà ati ìyan kì yio wá sori ilẹ yi; nipa idà, pẹlu ìyan, ni awọn woli wọnyi yio ṣegbe. 16 Ati awọn enia ti nwọn nsọ asọtẹlẹ fun ni a o lù bolẹ ni ita Jerusalemu, nitori ìyan ati idà, nwọn kì yio ri ẹniti o sin wọn, awọn aya wọn, ati ọmọkunrin wọn, ati ọmọbinrin wọn: nitoriti emi o tu ìwa-buburu wọn jade sori wọn. 17 Ki iwọ ki o si sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe: oju mi sun omije li oru ati li ọsan, kì yio si dá, nitoriti a ti ṣa wundia ọmọbinrin enia mi li ọgbẹ nla kikoro gidigidi ni lilù na. 18 Bi emi ba jade lọ si papa, sa wò o, a ri awọn ti a fi idà pa! bi emi ba si wọ inu ilu lọ, sa wò o, awọn ti npa ọ̀kakà ikú nitori iyan! nitori awọn, ati awọn woli, ati awọn alufa nwọ́ lọ si ilẹ ti nwọn kò mọ̀.

Àwọn Eniyan náà Bẹ OLUWA

19 Iwọ ha ti kọ̀ Juda silẹ patapata? ọkàn rẹ ti korira Sioni? ẽṣe ti iwọ ti lù wa, ti imularada kò si fun wa? awa nreti alafia, kò si si rere, ati fun igba imularada, ṣugbọn wò o, idãmu! 20 Awa jẹwọ iwa buburu wa, Oluwa, ati aiṣedede awọn baba wa: nitori awa ti ṣẹ̀ si ọ. 21 Máṣe korira wa, nitori orukọ rẹ, máṣe gan itẹ́ ogo rẹ, ranti, ki o máṣe dà majẹmu ti o ba wa dá. 22 Ẹniti o le mu ojo rọ̀ ha wà lọdọ awọn oriṣa awọn keferi? tabi ọrun le rọ̀ òjo? iwọ ha kọ́, Oluwa Ọlọrun wa? awa si nreti rẹ: nitori iwọ li o da gbogbo nkan wọnyi.

Jeremiah 15

Ìparun Yóo Dé Bá Àwọn Ọmọ Juda

1 OLUWA si wi fun mi pe, Bi Mose ati Samueli duro niwaju mi, sibẹ inu mi kì yio si yipada si awọn enia yi: ṣá wọn tì kuro niwaju mi, ki nwọn o si jade lọ. 2 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, nibo ni awa o jade lọ? ki iwọ ki o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; awọn ti ikú, si ikú, awọn ti idà, si idà; ati awọn ti ìyan, si ìyan, ati awọn ti igbèkun si igbèkun. 3 Emi si fi iru ijiya mẹrin sori wọn, li Oluwa wi, idà lati pa, ajá lati wọ́ kiri, ẹiyẹ oju-ọrun ati ẹranko ilẹ, lati jẹ, ati lati parun. 4 Emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, nitori Manasse, ọmọ Hesekiah, ọba Juda, nitori eyiti o ti ṣe ni Jerusalemu. 5 Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ. 6 Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu. 7 Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀. 8 Awọn opo rẹ̀ o di pipọ ju iyanrin eti okun: emi o mu arunni wa sori wọn, sori iyá ati ọdọmọkunrin li ọjọkanri; emi o mu ifoya ati ìbẹru nla ṣubu lu wọn li ojiji. 9 Ẹniti o bi meje nṣọ̀fọ o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ; õrùn rẹ̀ wọ̀ l'ọsan, oju ntì i, o si ndamu: iyoku ninu wọn l'emi o si fifun idà niwaju awọn ọta wọn, li Oluwa wi.

Jeremiah Ráhùn sí OLUWA

10 Egbe ni fun mi, iyá mi, ti o bi mi ni ọkunrin ija ati ijiyan gbogbo aiye! emi kò win li elé, bẹ̃ni enia kò win mi li elé; sibẹ gbogbo wọn nfi mi ré. 11 Oluwa ni, Emi kì o tú ọ silẹ fun rere! emi o mu ki ọta ki o bẹ̀ ọ ni ìgba ibi ati ni ìgba ipọnju! 12 A ha le ṣẹ irin, irin ariwa, ati idẹ bi? 13 Ohun-ini ati iṣura rẹ li emi o fi fun ijẹ, li aigbowo, nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ ni àgbegbe rẹ. 14 Emi o si mu ki awọn ọta rẹ kó wọn lọ si ilẹ ti iwọ kò mọ̀: nitoriti iná njo ni ibinu mi, ti yio jo lori rẹ. 15 Oluwa, iwọ mọ̀, ranti mi, bẹ̀ mi wò, ki o si gbẹsan mi lara awọn oninunibini mi! máṣe mu mi kuro nitori ipamọra rẹ: mọ̀ pe, mo ti jiya itiju nitori rẹ! 16 Nigbati a ri ọ̀rọ rẹ, emi si jẹ wọn, ọ̀rọ rẹ si jẹ inu didùn mi, nitori orukọ rẹ li a fi npè mi, iwọ Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun! 17 Emi kò joko ni ajọ awọn ẹlẹgan! ki emi si ni ayọ̀; mo joko emi nikan, nitori ọwọ rẹ: nitori iwọ ti fi ibanujẹ kún mi. 18 Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro? 19 Nitorina, bayi li Oluwa wi, Bi iwọ ba yipada, nigbana li emi o si tun mu ọ pada wá, iwọ o si duro niwaju mi: bi iwọ ba si yà eyi ti iṣe iyebiye kuro ninu buburu, iwọ o dabi ẹnu mi: nwọn o si yipada si ọ; ṣugbọn iwọ máṣe yipada si wọn. 20 Emi o si ṣe ọ fun awọn enia yi bi odi idẹ ati alagbara: nwọn o si ba ọ jà, ṣugbọn nwọn kì yio le bori rẹ, nitori emi wà pẹlu rẹ, lati gbà ọ là ati lati gbà ọ silẹ, li Oluwa wi. 21 Emi o si gba ọ silẹ kuro lọwọ awọn enia buburu, emi o si rà ọ pada kuro lọwọ awọn ìka.

Jeremiah 16

Ìfẹ́ OLUWA ní Ìgbésí Ayé Jeremiah

1 Ọ̀RỌ Oluwa tọ̀ mi wá wipe: 2 Iwọ kò gbọdọ ni aya, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ni ihinyi. 3 Nitori bayi li Oluwa wi niti ọmọkunrin ati ọmọbinrin ti a bi ni ihinyi, ati niti awọn iya wọn ti o bi wọn, ati niti awọn baba wọn ti o bi wọn ni ilẹ yi. 4 Nwọn o kú ikú àrun; a kì yio ṣọ̀fọ wọn; bẹ̃ni a kì yio si sin wọn; nwọn o si di àtan lori ilẹ: a o fi idà ati ìyan run wọn, ati okú wọn yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ. 5 Nitori bayi li Oluwa wi, máṣe wọ inu ile ãwẹ̀, bẹ̃ni ki iwọ máṣe lọ sọ̀fọ, tabi lọ pohùnrere ẹkun wọn; nitori emi ti mu alafia mi kuro lọdọ enia yi, li Oluwa wi, ani ãnu ati iyọ́nu. 6 Ati ẹni-nla ati ẹni-kekere yio kú ni ilẹ yi, a kì yio sin wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio fá ori wọn nitori wọn. 7 Bẹ̃ni ẹnikan kì yio bu àkara lati ṣọ̀fọ fun wọn, lati tù wọn ninu nitori okú; bẹ̃ni ẹnikan kì yio fun wọn ni ago itunu mu nitori baba wọn, tabi nitori iya wọn. 8 Iwọ kò gbọdọ lọ sinu ile àse, lati joko pẹlu wọn lati jẹ ati lati mu. 9 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo dakẹ ni ihinyi loju nyin ati li ọjọ nyin. 10 Yio si ṣe, nigbati iwọ o ba fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi han enia yi, nwọn o wi fun ọ pe, Ẽṣe ti Oluwa fi sọ̀rọ gbogbo ohun buburu nla yi si wa, tabi kini aiṣedede wa? tabi ẹ̀ṣẹ kini awa da si Oluwa Ọlọrun wa? 11 Nigbana ni iwọ o wi fun wọn pe, Nitoripe awọn baba nyin ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, ti nwọn si rìn tọ̀ ọlọrun miran lọ, ti nwọn si sìn wọn, ti nwọn si foribalẹ fun wọn, ti nwọn kọ̀ mi silẹ, ti nwọn kò pa ofin mi mọ; 12 Ati pẹlu pe, ẹnyin ti ṣe buburu jù awọn baba nyin lọ: nitorina sa wò o, ẹnyin rìn olukuluku nyin, ni agidi ọkàn buburu rẹ̀, ki ẹnyin ki o má ba gbọ́ temi: 13 Emi o si ta nyin nu kuro ni ilẹ yi, sinu ilẹ ti ẹnyin kò mọ̀, ẹnyin tabi awọn baba nyin, nibẹ li ẹnyin o sin ọlọrun miran, lọsan ati loru nibiti emi kì yio ṣe oju-rere fun nyin.

Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn

14 Nitorina, sa wò o, Bayi li Oluwa wi, ọjọ mbọ̀, ti a kì o wi mọ́ pe, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti; 15 Ṣugbọn, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade wá kuro ni ilẹ ariwa, ati kuro ni ilẹ nibiti o ti lé wọn si: emi o si tun mu wọn wá si ilẹ wọn, eyiti mo fi fun awọn baba wọn.

Ìjìyà Tí ń Bọ̀

16 Sa wò o, emi o ran apẹja pupọ, li Oluwa wi, nwọn o si dẹ wọn: lẹhin eyini, emi o rán ọdẹ pupọ, nwọn o si dẹ wọn lati ori oke-nla gbogbo, ati ori oke kekere gbogbo, ati lati inu palapala okuta jade. 17 Nitoriti oju mi mbẹ lara ọ̀na wọn gbogbo: nwọn kò pamọ kuro niwaju mi, bẹ̃ni ẹ̀ṣẹ wọn kò farasin kuro li oju mi. 18 Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.

Adura Igbẹkẹ le Jeremiah ninu OLUWA

19 Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn! 20 Enia lè ma dá ọlọrun fun ara rẹ̀: nitori awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun? 21 Nitorina, sa wò o, emi o mu ki nwọn ki o mọ̀, lẹ̃kan yi, emi o si mu ki nwọn ki o mọ̀ ọwọ mi ati ipa mi; nwọn o si mọ̀ pe, orukọ mi ni JEHOFA.

Jeremiah 17

Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Juda

1 Ẹ̀ṢẸ Juda ni a fi kalamu irin kọ, a fi ṣonṣo okuta adamante gbẹ ẹ sori walã aiya wọn, ati sori iwo pẹpẹ nyin. 2 Bi awọn ọmọ wọn ba ranti pẹpẹ wọn, ati ere òriṣa wọn, lẹba igi tutu, ati ibi giga wọnni. 3 Oke mi ti o wà ni papa! emi o fi ohun-ini rẹ pẹlu ọrọ̀ rẹ gbogbo fun ijẹ, ati ibi giga rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ yi gbogbo àgbegbe rẹ ka. 4 Iwọ fun ara rẹ ni yio jọ̃ ogún rẹ lọwọ, ti mo ti fi fun ọ, emi o mu ọ sìn awọn ọta rẹ ni ilẹ ti iwọ kò mọ̀ ri: nitoriti ẹnyin ti tinabọ ibinu mi, ti yio jo lailai.

Oríṣìíríṣìí Ọ̀rọ̀

5 Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rẹ̀, ẹniti ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ Oluwa! 6 Nitoripe yio dabi alaini ni aginju, ti kò si ri pe rere mbọ̀: ṣugbọn yio gbe ibi iyangbẹ ilẹ wọnni ni aginju, ilẹ iyọ̀ ti a kì igbe inu rẹ̀. 7 Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀! 8 Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso. 9 Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ? 10 Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀. 11 Bi aparo ti isaba lori ẹyin ti kò yin, bẹ̃ gẹgẹ ni ẹniti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì iṣe ni ododo; yio fi i silẹ lagbedemeji ọjọ rẹ̀, ati ni opin rẹ̀ yio jẹ aṣiwere. 12 Itẹ́ ogo! ibi giga lati ipilẹsẹ ni ibi ile mimọ́ wa! 13 Oluwa ni ireti Israeli! gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ yio dãmu, awọn ti o yẹ̀ kuro lọdọ mi, ni a o kọ orukọ wọn sinu ẽkuru, si ori ilẹ, nitori nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, orisun omi ìye.

Jeremiah Bèèrè fún Ìrànlọ́wọ́ OLUWA

14 Wò mi sàn, Oluwa, emi o si sàn! gbà mi là, emi o si là, nitori iwọ ni iyìn mi! 15 Sa wò o, nwọn wi fun mi pe, Nibo ni ọ̀rọ Oluwa wà? jẹ ki o wá wayi. 16 Bi o ṣe ti emi ni, emi kò yara kuro ki emi má ṣe oluṣọ-agutan, lẹhin rẹ, bẹ̃ni emi kò bere ọjọ ipọnju, iwọ mọ̀: eyiti o jade li ète mi, o ti hàn niwaju rẹ. 17 Máṣe di ibẹ̀ru fun mi! iwọ ni ireti mi li ọjọ ibi! 18 Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.

Pípa Ọjọ́ Ìsinmi Mọ́

19 Bayi li Oluwa wi fun mi; Lọ, ki o si duro ni ẹnu-ọ̀na awọn enia nibi ti awọn ọba Juda nwọle, ti nwọn si njade, ati ni gbogbo ẹnu-bode Jerusalemu. 20 Ki o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda ati gbogbo Juda, ati gbogbo ẹnyin olugbe Jerusalemu, ti o nkọja ninu ẹnu-bode wọnyi. 21 Bayi li Oluwa wi, Ẹ kiyesi li ọkàn nyin, ki ẹ máṣe ru ẹrù li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe mu u wá ninu ẹnu-bode Jerusalemu: 22 Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin. 23 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, nwọn kò si tẹti silẹ, nwọn mu ọrun wọn le, ki nwọn ki o má ba gbọ́, ati ki nwọn o má bà gba ẹ̀kọ́. 24 Yio si ṣe bi ẹnyin ba tẹtisilẹ gidigidi si mi, li Oluwa wi, ti ẹ kò ba ru ẹrù kọja ni ẹnu-bode ilu yi li ọjọ isimi, ti ẹ ba si yà ọjọ isimi si mimọ, ti ẹ kò si ṣe iṣẹkiṣẹ ninu rẹ̀, 25 Nigbana ni nwọn o wọ ẹnu-bode ilu yi, ani ọba, ati ijoye ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn ti ngun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, awọn wọnyi pẹlu ijoye wọn, awọn ọkunrin Juda, ati olugbe Jerusalemu: nwọn o si ma gbe ilu yi lailai. 26 Nwọn o si wá lati ilu Juda wọnni, ati lati àgbegbe Jerusalemu yikakiri, ati lati ilẹ Benjamini, lati pẹtẹlẹ, ati lati oke, ati lati gusu wá, nwọn o si mu ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹran ati turari, ati awọn wọnyi ti o mu iyìn wá si ile Oluwa. 27 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, lati ya ọjọ isimi si mimọ́, ti ẹ kò si ru ẹrù, ti ẹ kò tilẹ wọ ẹnu-bode Jerusalemu li ọjọ isimi; nigbana ni emi o da iná ni ẹnu-bode wọnni, yio si jo ãfin Jerusalemu run, a kì o si pa a.

Jeremiah 18

Jeremiah nílé Amọ̀kòkò

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ̀ Oluwa wipe, 2 Dide, sọkalẹ lọ si ile amọkoko, nibẹ li emi o mu ọ gbọ́ ọ̀rọ mi. 3 Mo si sọkalẹ lọ si ile amọkoko, sa wò o, o mọ iṣẹ kan lori kẹ̀kẹ. 4 Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ. 5 Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, 6 Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli. 7 Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run. 8 Bi orilẹ-ède na ti mo ti sọ ọ̀rọ si ba yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀, emi o yi ọkàn mi pada niti ibi ti emi ti rò lati ṣe si wọn. 9 Ati lojukanna ti emi sọ ọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan, lati tẹ̀ ẹ do ati lati gbìn i. 10 Bi o ba ṣe ibi niwaju mi, ti kò si gbà ohùn mi gbọ́: nigbana ni emi o yi ọkàn mi pada niti rere, eyiti mo wi pe, emi o ṣe fun wọn. 11 Njẹ nisisiyi, sa sọ fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi npete ibi si nyin, emi si nṣe ipinnu kan si nyin, si yipada, olukuluku kuro ninu ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun ọ̀na ati iṣe nyin ṣe rere. 12 Nwọn si wipe: Lasan ni: nitori awa o rìn nipa ipinnu wa, olukuluku yio si huwa agidi ọkàn buburu rẹ̀.

Àwọn Eniyan náà kọ OLUWA Sílẹ̀

13 Nitorina bayi li Oluwa wí, Ẹ sa bère ninu awọn orilẹ-ède, tani gbọ́ iru ohun wọnni: wundia Israeli ti ṣe ohun kan ti o buru jayi. 14 Omi ojo-didì Lebanoni yio ha dá lati ma ṣàn lati apata oko? tabi odò ti o jina, ti o tutu, ti o nṣan, yio ha gbẹ bi? 15 Nitoripe awọn enia mi gbàgbe mi, nwọn ti sun turari fun ohun asan, nwọn si ti mu ki nwọn ki o ṣubu loju ọ̀na wọn, ni ipa igbãni; lati rìn ni ipa ti a kò tẹ́. 16 Lati sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹ̀gan lailai; olukuluku ẹniti o ba kọja nibẹ, yio dãmu yio mì ori rẹ̀ si i. 17 Emi o tú wọn ka gẹgẹ bi ẹ̀fufu ila-õrùn niwaju ọta wọn; emi o kọ ẹ̀hin mi si wọn, kì yio ṣe oju mi, ni ọjọ iparun wọn.

Wọ́n Gbìmọ̀ Ibi sí Jeremiah

18 Nigbana ni nwọn wipe, Wá, ẹ jẹ ki a pinnu ìwa ibi si Jeremiah, nitori ofin kì yio ṣegbe lọwọ alufa, tabi igbimọ lọwọ ọlọgbọ́n, tabi ọ̀rọ lọwọ woli: ẹ wá, ẹ jẹ ki a fi ahọn wa lù u, ki a má si kiyesi ohun kan ninu ọ̀rọ rẹ̀. 19 Kiyesi mi, Oluwa, ki o si gbọ́ ohùn awọn ti nni mi lara. 20 A ha le fi ibi san rere? nitori nwọn ti wà iho fun ẹmi mi. Ranti pe emi ti duro niwaju rẹ lati sọ ohun rere nipa ti wọn, ati lati yi ibinu rẹ kuro lọdọ wọn. 21 Nitorina, fi awọn ọmọ wọn fun ìyan, ki o si fi idà pa wọn, jẹ ki aya wọn ki o di alailọmọ ati opó: ki a si fi ìka pa awọn ọkunrin wọn, jẹ ki a fi idà pa awọn ọdọmọde wọn li ogun. 22 Jẹ ki a gbọ́ igbe lati ilẹ wọn, nigbati iwọ o mu ẹgbẹ kan wá lojiji sori wọn: nitori nwọn ti wà ihò lati mu mi, nwọn si dẹ okùn fun ẹsẹ mi. 23 Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ mọ̀ gbogbo igbimọ wọn si mi lati pa mi, máṣe bò ẹbi wọn mọlẹ, bẹ̃ni ki iwọ máṣe pa ẹṣẹ wọn rẹ́ kuro niwaju rẹ, jẹ ki nwọn ki o ṣubu niwaju rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe si wọn ni ọjọ ibinu rẹ.

Jeremiah 19

Ìgò Amọ̀ Tí Ó Fọ́

1 BAYI li Oluwa wi, Lọ, rà igo amọ ti amọkoko, si mu ninu awọn àgba enia, ati awọn àgba alufa; 2 Ki o si lọ si afonifoji ọmọ Hinnomu ti o wà niwaju ẹnu-bode Harsiti, nibẹ ni ki o si kede gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ. 3 Ki o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda, ati olugbe Jerusalemu; Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi: sa wò o, emi o mu ibi wá sihin yi, eyiti eti gbogbo awọn ti o ba gbọ́ ọ, yio ho. 4 Nitori nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn ti sọ ihín yi di iyapa, nwọn si ti sun turari ninu rẹ̀ fun awọn ọlọrun miran, eyiti awọn, tabi awọn baba wọn kò mọ̀ ri, tabi awọn ọba Juda, nwọn si ti fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ kún ibi yi; 5 Nwọn ti kọ́ ibi giga fun Baali pẹlu, lati fi iná sun ọmọkunrin wọn, bi ẹbọ-ọrẹ sisun fun Baali, eyiti emi kò pa laṣẹ lati ṣe, ti emi kò si sọ, tabi ti kò si ru soke ninu mi: 6 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, a kì yio pe orukọ ibi yi ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn Afonifoji ipakupa. 7 Emi o sọ igbimọ Juda ati Jerusalemu di asan ni ibi yi; emi o mu ki nwọn ki o ṣubu niwaju ọta wọn, ati lọwọ awọn ti o nwá ẹmi wọn, okú wọn ni a o fi fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko ilẹ fun onjẹ. 8 Emi o si sọ ilu yi di ahoro, ati ẹ̀gan, ẹnikẹni ti o ba nkọja lọ nibẹ yio dãmu, yio si poṣe nitori gbogbo ìna rẹ̀. 9 Emi o si mu ki nwọn ki o jẹ ẹran-ara awọn ọmọkunrin wọn, ati ẹran-ara awọn ọmọbinrin wọn, ati ẹnikini wọn yio jẹ ẹran-ara ẹnikẹji ni igba idoti ati ihamọ, ti awọn ọta wọn, ati awọn ti o nwá ẹmi wọn yio ha wọn mọ. 10 Nigbana ni iwọ o fọ igo na li oju awọn ti o ba ọ lọ. 11 Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Bẹ̃ gẹgẹ li emi o fọ enia yi ati ilu yi, bi a ti ifọ ohun-èlo amọkoko, ti ẹnikan kò le tun ṣe mọ, nwọn o si sin wọn ni Tofeti, nitoriti aye kò si lati sinkú. 12 Bayi li emi o ṣe si ibi yi, li Oluwa wi, ati si olugbe inu rẹ̀, emi o tilẹ ṣe ilu yi bi Tofeti: 13 Gbogbo ile Jerusalemu ati ile awọn ọba Juda ni a o sọ di alaimọ́ bi Tofeti, gbogbo ile wọnni, lori orule eyiti a ti sun turari fun ogun ọrun, ti a si ru ẹbọ mimu fun ọlọrun miran. 14 Nigbana ni Jeremiah wá si Tofeti, nibiti Oluwa ti rán a lati sọ asọtẹlẹ; o si duro ni àgbala ile Oluwa; o si wi fun gbogbo awọn enia pe, 15 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu wá sori ilu yi, ati sori ileto rẹ̀ gbogbo ibi ti mo ti sọ si i, nitori ti nwọn ti wà ọrun kì, ki nwọn ki o má bà gbọ́ ọ̀rọ mi.

Jeremiah 20

Ìjà láàrin Jeremiah ati Paṣuri Alufaa

1 NJẸ Paṣuri, ọmọ Immeri, alufa, ti iṣe olori olutọju ni ile Oluwa, gbọ́ pe, Jeremiah sọ asọtẹlẹ ohun wọnyi. 2 Nigbana ni Paṣuri lù Jeremiah, woli, o si kàn a li àba ti o wà ni ẹnu-ọ̀na Benjamini, ti o wà li òke ti o wà lẹba ile Oluwa. 3 O si ṣe ni ọjọ keji, Paṣuri mu Jeremiah kuro ninu àba. Nigbana ni Jeremiah wi fun u pe, Oluwa kò pe orukọ rẹ ni Paṣuri (ire-yika-kiri), bikoṣe Magori-missa-bibu (idãmu-yika-kiri.) 4 Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ọ le idãmu lọwọ, pẹlu gbogbo awọn ọrẹ rẹ, nwọn o ṣubu nipa idà awọn ọta wọn, oju rẹ yio si ri i, emi o si fi gbogbo Juda le ọwọ ọba Babeli, on o si mu wọn lọ ni igbèkun si Babeli, yio si fi idà pa wọn. 5 Pẹlupẹlu emi o fi ọrọ̀ ilu yi, pẹlu ẽre rẹ̀ ati ohun iyebiye rẹ̀, ati gbogbo iṣura awọn ọba Juda li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ti yio jẹ wọn ti yio si mu wọn lọ si Babeli. 6 Ati iwọ, Paṣuri, ati gbogbo awọn ti o ngbe inu ile rẹ ni yio lọ si igbekun, iwọ o wá si Babeli, ati nibẹ ni iwọ o kú si, a o si sin ọ sibẹ, iwọ ati gbogbo ọrẹ rẹ ti iwọ ti sọ asọtẹlẹ eke fun.

Ìráhùn Jeremiah sí OLUWA

7 Oluwa, iwọ ti fi ọ̀rọ rọ̀ mi, emi si gba rirọ̀! iwọ li agbara jù mi lọ, o si bori mi; emi di ẹni iyọ-ṣuti-si lojojumọ, gbogbo wọn ni ngàn mi! 8 Nitori lati igba ti mo ti sọ̀rọ, emi kigbe, mo ke, Iwa-agbara, ati iparun, nitori a sọ ọ̀rọ Oluwa di ohun ẹ̀gan ati itiju fun mi lojojumọ. 9 Nitorina mo si wipe, emi kì yio mu ni ranti rẹ̀, emi kì yio si sọ ọ̀rọ li orukọ rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ rẹ̀ mbẹ bi iná ti njó ninu mi ti a se mọ inu egungun mi, o si rẹ̀ mi lati pa a mọra, emi kò le ṣe e. 10 Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀. 11 Ṣugbọn Oluwa mbẹ lọdọ mi bi akọni ẹlẹrù, nitorina awọn ti nṣe inunibini si mi yio ṣubu, nwọn kì yio le bori: oju yio tì wọn gidigidi, nitoripe nwọn kì o ṣe rere: a ki yio gbagbe itiju wọn lailai! 12 Oluwa awọn ọmọ-ogun, iwọ ti ndán olododo wò, iwọ si ri inu ati ọkàn, emi o ri ẹsan rẹ lara wọn: nitoriti mo ti fi ọ̀ran mi le ọ lọwọ! 13 Ẹ kọrin si Oluwa, ẹ yìn Oluwa, nitoriti o ti gbà ọkàn talaka kuro lọwọ awọn oluṣe buburu. 14 Egbe ni fun ọjọ na ti a bi mi! ọjọ na ti iya mi bi mi, ki o má ri ibukun! 15 Egbe ni fun ọkunrin na ti o mu ihìn tọ̀ baba mi wá, wipe, Ọmọkunrin li a bi fun ọ; o mu u yọ̀. 16 Ki ọkunrin na ki o si dabi ilu wọnni ti Oluwa ti bì ṣubu, li aiyi ọkàn pada, ki o si gbọ́ ẹkun li owurọ, ati ọ̀fọ li ọsangangan. 17 Nitoriti kò pa mi ni inu iya mi, tobẹ̃ ki iya mi di isà mi, ki o loyun mi lailai. 18 Ẽṣe ti emi fi jade kuro ninu iya mi, lati ri irora ati oṣi, ati lati pari ọjọ mi ni itiju?

Jeremiah 21

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìṣubú Jerusalẹmu

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa nigbati Sedekiah, ọba, ran Paṣuru, ọmọ Melkiah, ati Sefaniah, ọmọ Maaseah, alufa, wipe, 2 Bère, emi bẹ ọ, lọdọ Oluwa fun wa; nitori Nebukadnessari, ọba Babeli, ṣi ogun tì wa; bọya bi Oluwa yio ba wa lò gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀, ki on ki o le lọ kuro lọdọ wa. 3 Nigbana ni Jeremiah wi fun wọn pe, Bayi li ẹnyin o wi fun Sedekiah. 4 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: wõ, emi o yi ihamọra ogun ti o wà ni ọwọ nyin pada, eyiti ẹnyin nfi ba ọba Babeli, ati awọn ara Kaldea jà, ti o dotì nyin lẹhin odi, emi o kó wọn jọ si ãrin ilu yi. 5 Emi tikarami yio fi ọwọ ninà ati apa lile ba nyin jà, pẹlupẹlu ni ibinu, ati ni ikannu pẹlu ibinu nla. 6 Emi o si pa awọn olugbe ilu yi, enia pẹlu ẹranko, nwọn o ti ipa àjakalẹ-arun nlanla kú. 7 Lẹhin eyi, li Oluwa wi, emi o fi Sedekiah, ọba Juda, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia, ati awọn ti o kù ni ilu yi lọwọ ajakalẹ-àrun ati lọwọ idà, ati lọwọ ìyan; emi o fi wọn le Nebukadnessari, ọba Babeli lọwọ, ati le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: yio si fi oju idà pa wọn; kì yio da wọn si, bẹ̃ni kì yio ni iyọ́nu tabi ãnu. 8 Ati fun enia yi ni ki iwọ ki o wipe, Bayi li Oluwa wi; Sa wò o, emi fi ọ̀na ìye ati ọ̀na ikú lelẹ niwaju nyin. 9 Ẹniti o ba joko ninu ilu yi, yio ti ipa idà kú, ati nipa ìyan ati nipa àjakalẹ-àrun: ṣugbọn ẹniti o ba jade ti o si ṣubu si ọwọ awọn ara Kaldea ti o dó tì nyin, yio yè, ẹmi rẹ̀ yio si dabi ijẹ fun u. 10 Nitori emi ti yi oju mi si ilu yi fun ibi, kì isi iṣe fun rere, li Oluwa wi: a o fi i le ọba Babeli lọwọ, yio fi iná kun u.

Ìdájọ́ lórí Ìdílé Ọba Juda

11 Ati fun ile ọba Juda; Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: 12 Ile Dafidi, Bayi li Oluwa wi, Mu idajọ ṣẹ li owurọ, ki o si gba ẹniti a lọ lọwọ gba kuro li ọwọ aninilara, ki ibinu mi ki o má ba jade bi iná, ki o má si jo ti kì o si ẹniti yio pa a, nitori buburu iṣe nyin. 13 Wò o, Emi doju kọ nyin, olugbe afonifoji, ati ti okuta pẹtẹlẹ, li Oluwa wi, ẹnyin ti o wipe, Tani yio kọlu wa? ati tani yio wọ̀ inu ibugbe wa? 14 Ṣugbọn emi o jẹ nyin niya gẹgẹ bi eso iṣe nyin, li Oluwa wi; emi o si da iná ninu igbo rẹ ki o le jo gbogbo agbegbe rẹ.

Jeremiah 22

Iṣẹ́ tí Jeremiah Jẹ́ fún Ìdílé Ọba Juda

1 BAYI li Oluwa wi, Sọkalẹ lọ si ile ọba Juda, ki o si sọ ọ̀rọ yi nibẹ. 2 Si wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ọba Juda, ti o joko ni itẹ Dafidi, iwọ, ati awọn iranṣẹ rẹ, ati awọn enia rẹ ti o wọle ẹnu-bode wọnyi. 3 Bayi li Oluwa wi; Mu idajọ ati ododo ṣẹ, ki o si gbà ẹniti a lọ lọwọ gbà kuro lọwọ aninilara, ki o máṣe fi agbara ati ìka lò alejo, alainibaba ati opó, bẹ̃ni ki o máṣe ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ nihinyi. 4 Nitori bi ẹnyin ba ṣe nkan yi nitõtọ, nigbana ni awọn ọba yio wọle ẹnu-bode ilu yi, ti nwọn o joko lori itẹ Dafidi, ti yio gun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati enia rẹ̀. 5 Ṣugbọn bi ẹnyin kì yio ba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, Emi fi emitikarami bura, li Oluwa wi, pe, ile yi yio di ahoro. 6 Nitori bayi li Oluwa wi fun ile ọba Juda; Gileadi ni iwọ si mi, ori Lebanoni: sibẹ, lõtọ emi o sọ ọ di aginju, ati ilu ti a kò gbe inu wọn. 7 Emi o ya awọn apanirun sọtọ fun ọ, olukuluku pẹlu ihamọra rẹ̀: nwọn o si ke aṣayan igi kedari rẹ lulẹ, nwọn o si sọ wọn sinu iná. 8 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio rekọja lẹba ilu yi, nwọn o wi, ẹnikan fun ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Oluwa ṣe bayi si ilu nla yi? 9 Nigbana ni nwọn o dahùn pe, nitoriti nwọn ti kọ̀ majẹmu Oluwa Ọlọrun wọn silẹ; ti nwọn fi ori balẹ fun ọlọrun miran, nwọn si sìn wọn.

Iṣẹ́ tí Jeremiah Jẹ́ Nípa Joahasi

10 Ẹ máṣe sọkun fun okú, bẹ̃ni ki ẹ máṣe pohùnrere rẹ̀, ṣugbọn ẹ sọkun ẹ̀dun fun ẹniti o nlọ, nitori kì yio pada wá mọ, kì yio si ri ilẹ rẹ̀ mọ. 11 Nitori bayi li Oluwa wi fun Ṣallumu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ti o jọba ni ipo Josiah, baba rẹ̀, ti o jade kuro nihin pe, On kì yio pada wá mọ. 12 Ṣugbọn yio kú ni ibi ti a mu u ni igbèkun lọ, kì yio si ri ilẹ yi mọ.

Iṣẹ́ Tí Jeremiah Jẹ́ nípa Jehoiakimu

13 Egbe ni fun ẹniti o kọ́ ilẹ rẹ̀, ti kì iṣe nipa ododo, ati iyẹwu rẹ̀, ti kì iṣe nipa ẹ̀tọ́: ti o lò iṣẹ ọwọ aladugbo rẹ̀ lọfẹ, ti kò fi ere iṣẹ rẹ̀ fun u. 14 Ti o wipe, emi o kọ ile ti o ni ibò fun ara mi, ati iyẹwu nla, ti o ke oju ferese fun ara rẹ̀, ti o fi igi kedari bò o, ti o si fi ajẹ̀ kùn u. 15 Iwọ o ha jọba, nitori iwọ fi igi kedari dije? baba rẹ kò ha jẹ, kò ha mu? o si ṣe idajọ ati ododo, nitorina o dara fun u. 16 O dajọ ọ̀ran talaka ati alaini; o dara fun u: bi ãti mọ̀ mi kọ́ eyi? li Oluwa wi. 17 Ṣugbọn oju rẹ̀ ati ọkàn rẹ kì iṣe fun ohunkohun bikoṣe ojukokoro rẹ, ati lati ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, ati lati ṣe ininilara ati agbara. 18 Nitorina bayi li Oluwa wi nitori Jehoiakimu ọmọ Josiah, ọba Juda, nwọn kì yio ṣọ̀fọ fun u, wipe, Oṣe! arakunrin mi! tabi Oṣe! arabinrin mi! nwọn kì o ṣọ̀fọ fun u pe, Oṣe, oluwa! tabi Oṣe, ọlọla! 19 A o sin i ni isinkú kẹtẹkẹtẹ, ti a wọ́ ti a si sọ junù kuro ni ẹnu-bode Jerusalemu.

Iṣẹ́ Tí Jeremiah Jẹ́ nípa Ohun Tí Yóo Ṣẹlẹ̀ sí

20 Goke lọ si Lebanoni, ki o si ke, ki o si gbe ohùn rẹ soke ni Baṣani, ki o kigbe lati Abarimu, nitori a ti ṣẹ́ gbogbo olufẹ rẹ tutu, 21 Emi ti ba ọ sọ̀rọ ni ìgba ire rẹ; iwọ wipe, emi kì yio gbọ́. Eyi ni ìwa rẹ lati igba ewe rẹ wá, ti iwọ kò si gba ohùn mi gbọ. 22 Ẹfũfu yio fẹ gbogbo oluṣọ-agutan rẹ lọ, ati awọn olufẹ rẹ yio lọ si ìgbekun: nitõtọ, ni wakati na ni oju yio tì ọ, iwọ o si dãmu nitori gbogbo buburu rẹ. 23 Iwọ, olugbe Lebanoni, ti o tẹ́ itẹ si ori igi kedari, iwọ o ti jẹ otoṣi to, nigbati irora ba deba ọ, irora bi obinrin ti nrọbi!

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Jehoiakini

24 Bi emi ti wà, li Oluwa wi, bi Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, tilẹ jẹ oruka-èdidi lọwọ ọtun mi, sibẹ̀ emi o fà ọ tu kuro nibẹ. 25 Emi o si fi ọ le ọwọ awọn ti o nwá ẹmi rẹ, ati le ọwọ ẹniti iwọ bẹ̀ru rẹ̀, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati ọwọ awọn ara Kaldea. 26 Emi o tì ọ sode, ati iya rẹ ti o bi ọ si ilẹ miran, nibiti a kò bi nyin si; nibẹ li ẹnyin o si kú. 27 Ṣugbọn ilẹ na ti ẹnyin fẹ li ọkàn nyin lati pada si, nibẹ ni ẹnyin kì o pada si mọ. 28 Ọkunrin yi, Koniah, ohun-èlo ẹlẹgan, fifọ ha ni bi? o ha dabi ohun-èlo ti kò ni ẹwà lara? ẽṣe ti a tì wọn jade, on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ti a si le wọn jade si ilẹ ti nwọn kò mọ̀? 29 Ilẹ! ilẹ! ilẹ! gbọ́ ọ̀rọ Oluwa! 30 Bayi li Oluwa wi, Ẹ kọwe pe, ọkunrin yi alailọmọ ni, ẹniti kì yio ri rere li ọjọ aiye rẹ̀: nitori ọkan ninu iru-ọmọ rẹ̀ kì yio ri rere, ti yio fi joko lori itẹ Dafidi, ti yio si fi tun jọba lori Juda.

Jeremiah 23

Ìrètí Ọjọ́ Iwájú

1 EGBE ni fun awọn oluṣọ-agutan, ti nmu agbo-ẹran mi ṣìna, ti o si ntú wọn ka, li Oluwa wi. 2 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi si oluṣọ-agutan wọnni, ti nṣọ enia mi; Ẹnyin tú agbo-ẹran mi ká, ẹ le wọn junù, ẹnyin kò si bẹ̀ wọn wò, sa wò o, emi o bẹ̀ nyin wò nitori buburu iṣe nyin, li Oluwa wi. 3 Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i. 4 Emi o gbe oluṣọ-agutan dide fun wọn, ti yio bọ́ wọn: nwọn kì yio bẹ̀ru mọ́, tabi nwọn kì yio si dãmu, bẹ̃li ọkan ninu wọn kì yio si sọnu, li Oluwa wi. 5 Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na. 6 Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA. 7 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti: 8 Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.

Iṣẹ́ tí Jeremiah Jẹ́ nípa Àwọn Wolii

9 Si awọn woli. Ọkàn mi ti bajẹ ninu mi, gbogbo egungun mi mì; emi dabi ọmuti, ati ọkunrin ti ọti-waini ti bori rẹ̀ niwaju Oluwa, ati niwaju ọ̀rọ ìwa-mimọ́ rẹ̀. 10 Nitori ilẹ na kún fun awọn panṣaga; ilẹ na nṣọ̀fọ, nitori egún, pápá oko aginju gbẹ: irìn wọn di buburu, agbara wọn kò si to. 11 Nitori, ati woli ati alufa, nwọn bajẹ; pẹlupẹlu ninu ile mi ni mo ri ìwa-buburu wọn, li Oluwa wi. 12 Nitorina ipa-ọ̀na wọn yio jẹ fun wọn bi ibi yiyọ́ li okunkun: a o tì wọn, nwọn o si ṣubu ninu rẹ̀, nitori emi o mu ibi wá sori wọn, ani ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi. 13 Emi si ti ri were ninu awọn woli Samaria, nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ Baali, nwọn si mu Israeli enia mi ṣina. 14 Emi ti ri irira lara awọn woli Jerusalemu, nwọn ṣe panṣaga, nwọn si rìn ninu eke, nwọn mu ọwọ oluṣe-buburu le tobẹ̃, ti kò si ẹnikan ti o yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀; gbogbo wọn dabi Sodomu niwaju mi, ati awọn olugbe rẹ̀ bi Gomorra. 15 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti awọn woli; Sa wò o, emi o fi wahala bọ́ wọn, emi o si jẹ ki nwọn ki o mu omi orõro: nitori lati ọdọ awọn woli Jerusalemu ni ibajẹ ti jade lọ si gbogbo ilẹ na. 16 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ máṣe feti si ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin: nwọn sọ nyin di asan, nwọn sọ̀rọ iran inu ara wọn, kì iṣe lati ẹnu Oluwa. 17 Nwọn wi sibẹ fun awọn ti o ngàn mi pe, Oluwa ti wi pe, Alafia yio wà fun nyin; nwọn si wi fun olukuluku ti o nrìn nipa agidi ọkàn rẹ̀, pe, kò si ibi kan ti yio wá sori nyin. 18 Nitori tali o duro ninu igbimọ Oluwa, ti o woye, ti o si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀? tali o kíyesi ọ̀rọ rẹ̀, ti o si gbà a gbọ́? 19 Sa wò o, afẹfẹ-ìji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori awọn oluṣe buburu: 20 Ibinu Oluwa kì yio pada, titi yio fi ṣe e, titi yio si fi mu iro inu rẹ̀ ṣẹ, li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju. 21 Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọ̀rọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ. 22 Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn. 23 Emi ha iṣe Ọlọrun itosi? li Oluwa wi, kì iṣe Ọlọrun lati okere pẹlu? 24 Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi? 25 Emi ti gbọ́ eyiti awọn woli sọ, ti nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ mi wi pe, Mo lá alá! mo lá alá! 26 Yio ti pẹ to, ti eyi yio wà li ọkàn awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ eke? ani, awọn alasọtẹlẹ ẹ̀tan ọkàn wọn. 27 Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali. 28 Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi? 29 Ọ̀rọ mi kò ha dabi iná? li Oluwa wi; ati bi òlu irin ti nfọ́ apata tútu? 30 Nitorina sa wò o, emi dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti o nji ọ̀rọ mi, ẹnikini lati ọwọ ẹnikeji rẹ̀. 31 Sa wò o, emi o dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti nwọn lò ahọn wọn, ti nwọn nsọ jade pe: O wi. 32 Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.

Ẹrù OLUWA

33 Ati nigbati awọn enia yi, tabi woli, tabi alufa, yio bi ọ lere wipe, kini Ọ̀rọ-wuwo Oluwa? nigbana ni iwọ o wi fun wọn Ọ̀rọ-wuwo ni eyi pé: Emi o tì nyin jade, li Oluwa wi. 34 Ati woli, ati alufa, ati awọn enia, ti yio wipe, Ọ̀rọ-wuwo Oluwa, emi o jẹ oluwa rẹ̀ ati ile rẹ̀ ni ìya. 35 Bayi li ẹnyin o wi, ẹnikini fun ẹnikeji, ati ẹnikan fun arakunrin rẹ̀, pe Kini idahùn Oluwa? ati kini ọ̀rọ Oluwa? 36 Ẹ kì o si ranti ọ̀rọ-wuwo Oluwa mọ́, nitori ọ̀rọ olukuluku yio di ẹrù-wuwo fun ontikararẹ̀; nitori ti ẹnyin ti yi ọ̀rọ Ọlọrun alãye dà, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun wa. 37 Bayi ni iwọ o wi fun woli nì pe: Idahùn wo li Oluwa fi fun ọ? ati pẹlu; Kini Oluwa wi? 38 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa, nitorina, bayi li Oluwa wi, nitori ẹnyin nsọ ọ̀rọ yi pe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa ti emi si ranṣẹ si nyin pe ki ẹ máṣe wipe: ọ̀rọ-wuwọ Oluwa; 39 Nitorina, sa wò o, Emi o gbagbe nyin patapata, emi o si kọ̀ nyin silẹ, emi o si tì nyin jade, ati ilu ti mo fi fun nyin ati fun awọn baba nyin, kuro niwaju mi. 40 Emi o si mu ẹ̀gan ainipẹkun wá sori nyin, ati itiju lailai, ti a kì yio gbagbe.

Jeremiah 24

Apẹ̀rẹ̀ Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Meji

1 SI wò o, Oluwa fi agbọn eso-ọ̀pọtọ meji hàn mi, ti a gbe kalẹ niwaju ile Oluwa, lẹhin igbati Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni ìgbekun pẹlu awọn olori Juda, pẹlu awọn gbẹna-gbẹna, ati awọn alagbẹdẹ, lati Jerusalemu, ti o si mu wọn wá si Babeli. 2 Agbọn ikini ni eso-ọ̀pọtọ daradara jù, gẹgẹ bi eso ọ̀pọtọ ti o tetekọ pọ́n: agbọn ekeji ni eso-ọ̀pọtọ ti o buruju, ti a kò le jẹ, bi nwọn ti buru tó. 3 Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, Kini iwọ ri, Jeremiah? Emi wipe, Eso-ọ̀pọtọ, eyi ti o dara, dara jù, ati eyi ti o buru, buru jù, tobẹ̃ ti a kò le jẹ ẹ, nitori nwọn buru jù. 4 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, 5 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ daradara wọnyi, bẹ̃li emi o fi oju rere wò awọn ìgbekun Juda, ti emi ran jade kuro ni ibi yi lọ si ilẹ awọn ara Kaldea. 6 Emi o si kọju mi si wọn fun rere, emi o si mu wọn pada wá si ilẹ yi, emi o gbe wọn ró li aitun wó wọn lulẹ, emi o gbìn wọn, li aitun fà wọn tu. 7 Emi o si fun wọn li ọkàn lati mọ̀ mi, pe, Emi li Oluwa, nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nitoripe nwọn o fi gbogbo ọkàn wọn yipada si mi. 8 Ati gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ biburujù ti a kò le jẹ, nitoriti nwọn burujù, bayi li Oluwa wi, Bẹ̃ gẹgẹ ni emi o ṣe Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn ti o kù ni Jerusalemu, ati awọn iyokù ni ilẹ yi ati awọn ti ngbe ilẹ Egipti. 9 Emi o fi wọn fun iwọsi ati fun ibi ninu gbogbo ijọba aiye, lati di ìtiju, owe, ẹsin, ati ẹ̀gan ni ibi gbogbo, ti emi o le wọn si. 10 Emi o si rán idà, ìyan, ati ajakalẹ-arun, si ãrin wọn, titi nwọn o fi parun kuro ni ilẹ eyi ti emi fi fun wọn ati fun awọn baba wọn.

Jeremiah 25

Àwọn Ọ̀tá láti Ìhà Àríwá

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli. 2 Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe: 3 Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i. 4 Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́. 5 Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai. 6 Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi. 7 Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin. 8 Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi. 9 Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun. 10 Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn. 11 Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun ati ahoro: orilẹ-ède wọnyi yio si sìn ọba Babeli li ãdọrin ọdun. 12 Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai. 13 Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède. 14 Nitoriti awọn wọnyi pẹlu yio mu ki orilẹ-ède pupọ, ati awọn ọba nla sìn wọn: emi o san a fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn ati pẹlu gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn.

Ìdájọ́ OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-èdè náà

15 Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi fun mi: Gba ago ọti-waini ibinu mi yi kuro lọwọ mi, ki o si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède ti emi o rán ọ si, mu u. 16 Ki nwọn mu, ki nwọn si ma ta gbọ̀ngbọn, ki nwọn si di aṣiwere, nitori idà ti emi o rán si ãrin wọn. 17 Nigbana ni mo gba ago na li ọwọ Oluwa, emi si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède, ti Oluwa rán mi si, mu u. 18 Ani Jerusalemu ati ilu Juda wọnni, ati awọn ọba wọn pẹlu awọn ijoye, lati sọ wọn di ahoro, idãmu, ẹsin, ati egún, gẹgẹ bi o ti ri loni. 19 Farao, ọba Egipti, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo enia rẹ̀. 20 Ati gbogbo awọn enia ajeji, ati gbogbo ọba ilẹ Usi, gbogbo ọba ilẹ Filistia, ati Aṣkeloni, ati Gasa, ati Ekroni, ati awọn iyokù Aṣdodi, 21 Edomu, ati Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni, 22 Ati gbogbo awọn ọba Tire, ati gbogbo awọn ọba Sidoni, ati awọn ọba erekuṣu wọnni ti mbẹ ni ikọja okun, 23 Dedani, ati Tema, ati Busi, ati gbogbo awọn ti nda òṣu. 24 Ati gbogbo awọn ọba Arabia, pẹlu awọn ọba awọn enia ajeji ti ngbe inu aginju. 25 Ati gbogbo awọn ọba Simri, ati gbogbo awọn ọba Elamu, ati gbogbo awọn ọba Medea. 26 Ati gbogbo awọn ọba ariwa, ti itosi ati ti ọ̀na jijin, ẹnikini pẹlu ẹnikeji rẹ̀, ati gbogbo ijọba aiye, ti mbẹ li oju aiye, ọba Ṣeṣaki yio si mu lẹhin wọn. 27 Iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ mu, ki ẹ si mu amuyo, ki ẹ bì, ki ẹ si ṣubu, ki ẹ má si le dide mọ́, nitori idà ti emi o rán sãrin nyin. 28 Yio si ṣe, bi nwọn ba kọ̀ lati gba ago lọwọ rẹ lati mu, ni iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ni mimu ẹnyin o mu! 29 Sa wò o, nitori ti emi bẹrẹ si imu ibi wá sori ilu na ti a pè li orukọ mi, ẹnyin fẹ ijẹ alaijiya? ẹnyin kì yio ṣe alaijiya: nitori emi o pè fun idà sori gbogbo olugbe aiye, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 30 Njẹ iwọ sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Oluwa yio kọ lati oke wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ lati ibugbe rẹ̀ mimọ́, ni kikọ, yio kọ sori ibugbe rẹ̀, yio pariwo sori gbogbo olugbe aiye, bi awọn ti ntẹ ifunti. 31 Igbe kan yio wá titi de opin ilẹ aiye; nitori Oluwa ni ijà ti yio ba awọn orilẹ-ède ja, yio ba gbogbo ẹran-ara wijọ, yio fi awọn oluṣe-buburu fun idà, li Oluwa wi. 32 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, ibi yio jade lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ìji nlanla yio ru soke lati agbegbe aiye. 33 Awọn ti Oluwa pa yio wà li ọjọ na lati ipẹkun kini aiye titi de ipẹkun keji aiye, a kì yio ṣọ̀fọ wọn, a kì yio ko wọn jọpọ, bẹ̃ni a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan lori ilẹ. 34 Ke! ẹnyin oluṣọ-agutan! ki ẹ si sọkun! ẹ fi ara nyin yilẹ ninu ẽru, ẹnyin ọlọla agbo-ẹran! nitori ọjọ a ti pa nyin ati lati tú nyin ka pe, ẹnyin o si ṣubu bi ohun-elo iyebiye. 35 Sisa kì yio si fun awọn oluṣọ-agutan, bẹ̃ni asalà kì yio si fun awọn ọlọla agbo-ẹran. 36 Ohùn ẹkun awọn oluṣọ-agutan, ati igbe awọn ọlọla agbo-ẹran li a o gbọ́: nitori Oluwa bà papa-oko tutu wọn jẹ. 37 Ibùgbe alafia li o di ahoro, niwaju ibinu kikan Oluwa. 38 O ti fi pantiri rẹ̀ silẹ bi kiniun nitori ti ilẹ wọn di ahoro, niwaju ibinu idà aninilara, ati niwaju ibinu kikan rẹ̀.

Jeremiah 26

A Pe Jeremiah Lẹ́jọ́

1 NI ibẹrẹ ijọba Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ni ọ̀rọ yi ti ọdọ Oluwa wá wipe; 2 Bayi li Oluwa wi, Duro ni àgbala ile Oluwa, ki o si sọ fun gbogbo ilu Juda ti o wá lati sìn ni ile Oluwa gbogbo ọ̀rọ ti mo pa laṣẹ fun ọ lati sọ fun wọn: máṣe ke ọ̀rọ kanṣoṣo kù: 3 Bi o ba jẹ pe nwọn o gbọ́, ti olukuluku yio yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, ki emi ki o le yi ọkàn pada niti ibi ti emi rò lati ṣe si wọn, nitori iṣe buburu wọn. 4 Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi: bi ẹnyin kì yio feti si mi lati rin ninu ofin mi, ti emi ti gbe kalẹ niwaju nyin. 5 Lati gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, ti emi rán si nyin, ti mo ndide ni kutukutu, ti mo rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́. 6 Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye. 7 Nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia gbọ́, bi Jeremiah ti nsọ ọ̀rọ wọnyi ni ile Oluwa. 8 O si ṣe nigbati Jeremiah pari gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa paṣẹ fun u lati sọ fun gbogbo enia, nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia di i mu wipe, kikú ni iwọ o kú! 9 Ẽṣe ti iwọ sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa wipe, Ile yi yio dabi Ṣilo, ati ilu yi yio di ahoro laini olugbe? Gbogbo enia kojọ pọ̀ tì Jeremiah ni ile Oluwa. 10 Nigbati awọn ijoye Juda gbọ́ nkan wọnyi, nwọn jade lati ile ọba wá si ile Oluwa, nwọn si joko li ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa. 11 Awọn alufa ati awọn woli wi fun awọn ijoye, ati gbogbo enia pe, ọkunrin yi jẹbi ikú nitoriti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, bi ẹnyin ti fi eti nyin gbọ́. 12 Nigbana ni Jeremiah wi fun awọn ijoye ati gbogbo enia pe, Oluwa rán mi lati sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ́, si ile yi ati si ilu yi. 13 Njẹ nisisiyi, ẹ tun ọ̀na nyin ati iṣe nyin ṣe, ki ẹ si gbọ́ ohùn Oluwa Ọlọrun nyin; Oluwa yio si yi ọkàn rẹ̀ pada niti ibi ti o sọ si nyin. 14 Bi o ṣe ti emi, sa wò o, emi mbẹ li ọwọ nyin: ẹ ṣe si mi, gẹgẹ bi o ti dara ti o si yẹ loju nyin. 15 Sibẹ, ẹ mọ̀ eyi daju pe, bi ẹ ba pa mi, mimu ni ẹnyin o mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ wá sori nyin ati sori ilu yi, ati sori awọn olugbe rẹ̀: nitori li otitọ Oluwa li o rán mi si nyin lati sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi li eti nyin. 16 Nigbana ni awọn ijoye ati gbogbo enia sọ fun awọn alufa ati awọn woli pe, ọkunrin yi kò yẹ lati kú; nitoriti o sọ̀rọ fun wa li orukọ Oluwa, Ọlọrun wa. 17 Awọn ọkunrin kan ninu awọn àgba na si dide, nwọn si sọ fun gbogbo ijọ enia wipe: 18 Mikah, ara Moraṣi, ṣe woli li ọjọ Hesekiah, ọba Juda, o si wi fun gbogbo enia Juda pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: a o tulẹ Sioni fun oko, Jerusalemu yio di òkiti alapa, ati oke ile yi gẹgẹ bi ibi giga igbo. 19 Njẹ, Hesekiah, ọba Juda, ati gbogbo Juda ha pa a bi? Ẹ̀ru Oluwa kò ha bà a, kò ha bẹ Oluwa bi? Oluwa si yi ọkàn pada niti ibi ti o ti sọ si wọn; Bayi li awa iba ṣe mu ibi nla wá sori ẹmi wa? 20 Ọkunrin kan si wà ẹ̀wẹ, ti o sọ asọtẹlẹ ni orukọ Oluwa, ani Urijah, ọmọ Ṣemaiah, ara Kirjatjearimu, ti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, ati si ilẹ yi, gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ Jeremiah. 21 Ati nigbati Jehoiakimu, ọba, pẹlu gbogbo ọkunrin alagbara rẹ̀, ati awọn ijoye gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ọba nwá a lati pa; ṣugbọn nigbati Urijah gbọ́, o bẹ̀ru, o salọ o si wá si Egipti. 22 Jehoiakimu, ọba, si rán enia lọ si Egipti, ani Elnatani, ọmọ Akbori ati enia miran pẹlu rẹ̀ lọ si Egipti. 23 Nwọn si mu Urijah lati Egipti tọ Jehoiakimu ọba wá; ẹni ti o fi idà pa a, o si sọ okú rẹ̀ sinu isa-okú awọn enia lasan. 24 Bẹ̃ni ọwọ Ahikamu, ọmọ Safani mbẹ pẹlu Jeremiah, ki nwọn ki o má ba fi i le awọn enia lọwọ lati pa.

Jeremiah 27

A Pe Jeremiah Lẹ́jọ́

1 LI atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọ̀dọ Oluwa wipe, 2 Bayi li Oluwa wi fun mi; Ṣe ijara ati àjaga-ọrùn fun ara rẹ, ki o si fi wọ ọrùn rẹ. 3 Ki o rán wọn lọ si ọdọ ọba Edomu, ati si ọba Moabu, ati si ọba awọn ọmọ Ammoni, ati si ọba Tire, ati si ọba Sidoni, lọwọ awọn ikọ̀ ti o wá si Jerusalemu sọdọ Sedekiah, ọba Juda. 4 Ki o si paṣẹ fun wọn lati wi fun awọn oluwa wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Bayi li ẹnyin o wi fun awọn oluwa nyin pe; 5 Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi. 6 Njẹ nisisiyi, emi fi gbogbo ilẹ yi le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi: ati ẹranko igbẹ ni mo fi fun u pẹlu lati sin i. 7 Ati orilẹ-ède gbogbo ni yio sin on, ati ọmọ rẹ̀ ati ọmọ-ọmọ rẹ̀, titi di ìgba ti akoko ilẹ tirẹ̀ yio de; lara rẹ̀ ni orilẹ-ède pupọ ati awọn ọba nla yio jẹ. 8 Yio si ṣe, orilẹ-ède ati ijọba ti kì yio sin Nebukadnessari ọba Babeli, ti kì yio fi ọrùn wọn si abẹ àjaga ọba Babeli, orilẹ-ède na li emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, jẹ niya, li Oluwa wi, titi emi o fi run wọn nipa ọwọ rẹ̀. 9 Nitorina ẹ máṣe fi eti si awọn woli nyin, tabi si awọn alafọṣẹ nyin, tabi si awọn alála, tabi si awọn oṣo nyin, tabi awọn ajẹ nyin ti nsọ fun nyin pe, Ẹnyin kì o sin ọba Babeli: 10 Nitori nwọn sọ-asọtẹlẹ eke fun nyin, lati mu nyin jina réré kuro ni ilẹ nyin, ki emi ki o lè lé nyin jade, ti ẹnyin o si ṣegbe. 11 Ṣugbọn orilẹ-ède na ti o mu ọrùn rẹ̀ wá si abẹ àjaga ọba Babeli, ti o si sìn i, on li emi o jẹ ki o joko ni ilẹ wọn, li Oluwa wi, yio si ro o, yio si gbe ibẹ. 12 Emi si wi fun Sedekiah, ọba Juda, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi, pe, Ẹ mu ọrùn nyin si abẹ àjaga ọba Babeli, ki ẹ sin i, pẹlu awọn enia rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin o yè. 13 Ẽṣe ti ẹnyin o kú, iwọ, ati enia rẹ, nipa idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, bi Oluwa ti sọ si orilẹ-ède ti kì yio sin ọba Babeli. 14 Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin. 15 Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin. 16 Pẹlupẹlu emi sọ fun awọn alufa ati fun gbogbo enia yi wipe, Bayi li Oluwa wi, Ẹ má gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin wipe, Sa wò o, ohun-èlo ile Oluwa li a o mu pada li aipẹ nisisiyi lati Babeli wá: nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin. 17 Ẹ máṣe gbọ́ ti wọn; ẹ sin ọba Babeli, ẹ si yè: ẽṣe ti ilu yi yio fi di ahoro? 18 Ṣugbọn bi nwọn ba ṣe woli, ati bi ọ̀rọ Oluwa ba wà pẹlu wọn, jẹ ki nwọn ki o bẹbẹ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ki ohun-èlo iyokù ni ile Oluwa ati ni ile ọba Judah, ati ni Jerusalemu, ki nwọn ki o máṣe lọ si Babeli. 19 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti opó mejeji, ati niti agbada nla, ati niti ipilẹṣẹ, ati niti ohun-èlo iyokù ti o kù ni ilu yi. 20 Eyi ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kò mu lọ nigbati o mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli, pẹlu gbogbo awọn ọlọla Juda ati Jerusalemu; 21 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, niti ohun-èlo ti o kù ni ile Oluwa, ati ni ile ọba Juda ati Jerusalemu. 22 A o kó wọn lọ si Babeli, nibẹ ni nwọn o wà titi di ọjọ na ti emi o bẹ̀ wọn wò, li Oluwa wi, emi o si mu wọn goke wá, emi o si mu wọn pada wá si ibi yi.

Jeremiah 28

Wolii Jeremiah ati Wolii Hananaya

1 O si ṣe li ọdun kanna li atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, li ọdun kẹrin ati oṣù karun, ti Hananiah, ọmọ Asuri woli, ti iṣe ti Gibeoni, wi fun mi ni ile Oluwa, niwaju awọn alufa ati gbogbo enia pe, 2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Emi ti ṣẹ àjaga ọba Babeli. 3 Ninu akoko ọdun meji li emi o tun mu gbogbo ohun-èlo ile Oluwa pada wá si ibi yi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kó kuro ni ibi yi, ti o si mu wọn lọ si Babeli. 4 Emi o si tun mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pẹlu awọn igbekun Juda, ti o ti lọ si Babeli pada wá si ibi yi, li Oluwa wi, nitori emi o si ṣẹ àjaga ọba Babeli. 5 Jeremiah woli si wi fun Hananiah woli niwaju awọn alufa ati niwaju gbogbo enia, ti o duro ni ile Oluwa pe: 6 Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi. 7 Ṣugbọn nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ yi ti mo sọ si eti rẹ ati si eti enia gbogbo. 8 Awọn woli ti o ti ṣaju mi, ati ṣaju rẹ ni igbãni sọ asọtẹlẹ pupọ, ati si ijọba nla niti ogun, ati ibi, ati ajakalẹ-arun. 9 Woli nì ti o sọ asọtẹlẹ alafia, bi ọ̀rọ woli na ba ṣẹ, nigbana ni a o mọ̀ woli na pe, Oluwa rán a nitõtọ. 10 Nigbana ni Hananiah woli mu àjaga kuro li ọrùn Jeremiah woli o si ṣẹ́ ẹ. 11 Hananiah si wi niwaju gbogbo enia pe, Bayi li Oluwa wi; Bẹ̃ gẹgẹ li emi o ṣẹ́ ajaga Nebukadnessari, ọba Babeli, kuro li ọrùn orilẹ-ède gbogbo ni igba ọdun meji. Jeremiah woli si ba ọ̀na tirẹ̀ lọ. 12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah woli wá lẹhin igbati Hananiah woli ti ṣẹ́ ajaga kuro li ọrùn Jeremiah woli, wipe, 13 Lọ isọ fun Hananiah wipe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti ṣẹ́ àjaga igi; ṣugbọn iwọ o si ṣe àjaga irin ni ipo wọn. 14 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi: emi ti fi ajaga irin si ọrùn gbogbo orilẹ-ède wọnyi, ki nwọn ki o sin Nebukadnessari, ọba Babeli, nwọn o si sin i, emi si fi ẹranko igbẹ fun u pẹlu. 15 Nigbana ni Jeremiah, woli, wi fun Hananiah, woli, pe, Gbọ́ nisisiyi, Hananiah; Oluwa kò rán ọ; ṣugbọn iwọ jẹ ki enia yi ki o gbẹkẹle eke. 16 Nitorina bayi li Oluwa wi; Sa wo o, emi o ta ọ nù kuro loju aiye: li ọdun yi ni iwọ o kú, nitori iwọ ti sọ̀rọ iṣọtẹ si Oluwa. 17 Bẹ̃ni Hananiah woli si kú li ọdun na li oṣu keje.

Jeremiah 29

Lẹta Jeremiah sí Àwọn Tí Ogun Kó Lọ sí Babiloni

1 WỌNYI si li ọ̀rọ iwe ti Jeremiah woli rán lati Jerusalemu si iyokù ninu awọn àgba ti o wà ni igbèkun, ati si awọn alufa, ati awọn woli, ati si gbogbo enia ti Nebukadnessari kó ni igbekun lọ lati Jerusalemu si Babeli. 2 Lẹhin igbati Jekoniah, ọba, ati ayaba, ati awọn iwẹfa, ati awọn ijoye Juda ati Jerusalemu, ati awọn gbẹna-gbẹna pẹlu awọn alagbẹdẹ ti fi Jerusalemu silẹ lọ. 3 Nipa ọwọ Elasa, ọmọ Ṣafani, ati Gemariah, ọmọ Hilkiah, (ẹniti Sedekiah, ọba Juda, rán si Babeli tọ Nebukadnessari, ọba Babeli) wipe, 4 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi fun gbogbo awọn ti a kó ni igbekun lọ, ti emi mu ki a kó lọ lati Jerusalemu si Babeli; 5 Ẹ kọ́ ile ki ẹ si ma gbe inu wọn; ẹ gbìn ọgba, ki ẹ si mã jẹ eso wọn; 6 Ẹ fẹ́ aya, ki ẹ si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ si fẹ́ aya fun awọn ọmọ nyin, ẹ si fi awọn ọmọbinrin nyin fun ọkọ, ki nwọn ki o le mã bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ le mã pọ si i nibẹ, ki ẹ má si dínkù. 7 Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia. 8 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki awọn woli nyin ti o wà lãrin nyin ati awọn alafọṣẹ nyin tàn nyin jẹ, ki ẹ má si feti si alá nyin ti ẹnyin lá. 9 Nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi: emi kò rán wọn, li Oluwa wi. 10 Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi. 11 Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti. 12 Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin. 13 Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi. 14 Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ. 15 Nitoriti ẹnyin ti wipe, Oluwa ti gbe awọn woli kalẹ fun wa ni Babeli: 16 Pe, Bayi li Oluwa wi niti ọba ti o joko lori itẹ́ Dafidi, ati niti gbogbo enia, ti ngbe ilu yi, ani niti awọn arakunrin nyin ti kò jade lọ pẹlu nyin sinu igbekun. 17 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o rán idà sarin wọn, ìyan, ati àjakalẹ-àrun, emi o ṣe wọn bi eso-ọ̀pọtọ buburu, ti a kò le jẹ, nitori nwọn buru. 18 Emi o si fi idà, ìyan, ati àjakalẹ-arun lepa wọn; emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, fun egún, ati iyanu, ati ẹsin, ati ẹ̀gan, lãrin gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi o le wọn si. 19 Nitoriti nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ mi, li Oluwa wi, ti emi rán si wọn nipa awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, emi dide ni kutukutu mo si rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ igbọ́, li Oluwa wi. 20 Njẹ ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin igbekun ti emi ti ran jade lati Jerusalemu si Babeli. 21 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, niti Ahabu ọmọ Kolaiah, ati niti Sedekiah ọmọ Maaseiah, ti nsọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi; wò o, emi fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli; on o si pa wọn li oju nyin; 22 Ati lati ọdọ wọn li a o da ọ̀rọ-egún kan silẹ li ẹnu gbogbo igbekun Juda ti o wà ni Babeli, wipe; Ki Oluwa ki o ṣe ọ bi Sedekiah, ati bi Ahabu, awọn ẹniti ọba Babeli sun ninu iná. 23 Nitori nwọn ti hùwa wère ni Israeli, nwọn si ba aya aladugbo wọn ṣe panṣaga, nwọn si ti sọ̀rọ eke li orukọ mi, ti emi kò ti pa li aṣẹ fun wọn: emi tilẹ mọ̀, emi si li ẹlẹri, li Oluwa wi.

Ìwé Tí Ṣemaaya Kọ

24 Ati fun Ṣemaiah ara Nehalami, ni iwọ o sọ wipe. 25 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitoripe iwọ ti rán iwe li orukọ rẹ si gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu ati si Sefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, ati si gbogbo awọn alufa, wipe, 26 Oluwa ti fi ọ jẹ oyè alufa ni ipo Jehoiada, alufa, ki ẹnyin ki o lè jẹ olutọju ni ile Oluwa, nitori olukuluku aṣiwere enia, ati ẹnikẹni ti o sọ asọtẹlẹ ki iwọ ki o le fi wọn sinu tubu ati sinu àba. 27 Njẹ nisisiyi, ẽṣe ti iwọ kò ba Jeremiah ti Anatoti wi, ẹniti o nsọ asọtẹlẹ fun nyin! 28 Nitorina li o ṣe ranṣẹ si wa ni Babeli, wipe, Akoko yio pẹ: ẹ kọ́ ile, ki ẹ si ma gbe inu wọn, ẹ si gbìn ọgbà, ki ẹ ma jẹ eso wọn. 29 Sefaniah, alufa, si ka iwe yi li eti Jeremiah woli. 30 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá wipe, 31 Ranṣẹ si gbogbo awọn igbekun, wipe, Bayi li Oluwa wi niti Ṣemaiah, ara Nehalami, nitoripe Ṣemaiah ti sọtẹlẹ fun nyin, ṣugbọn emi kò ran a, ti on si mu nyin gbẹkẹle eke: 32 Nitorina, bayi li Oluwa wi: Wò o, emi o bẹ Ṣemaiah, ara Nehalami, wò, ati iru-ọmọ rẹ̀; on kì yio ni ọkunrin kan lati ma gbe ãrin enia yi; bẹ̃ni kì yio ri rere na ti emi o ṣe fun awọn enia mi, li Oluwa wi; nitoripe o ti ṣọ̀tẹ si Oluwa.

Jeremiah 30

Ìlérí OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe. 2 Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, pe, Iwọ kọ gbogbo ọ̀rọ ti mo ti ba ọ sọ sinu iwe kan. 3 Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu igbekun awọn enia mi, Israeli ati Juda, pada, li Oluwa wi: emi o si mu ki nwọn pada bọ̀ si ilẹ ti emi fi fun awọn baba wọn, nwọn o si ni i. 4 Wọnyi si li ọ̀rọ ti Oluwa sọ niti Israeli ati niti Juda. 5 Nitori bayi li Oluwa wi; Awa ti gbọ́ ohùn ìwa-riri, ẹ̀ru, kì si iṣe ti alafia. 6 Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkunrin a mã rọbi ọmọ: Ẽṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkunrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn, bi obinrin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro? 7 Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹ̃ ti kò si ọkan bi iru rẹ̀: o jẹ àkoko wahala fun Jakobu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ̀. 8 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi o si ṣẹ àjaga kuro li ọrùn rẹ, emi o si ja ìde rẹ, awọn alejo kì yio si mu ọ sìn wọn mọ: 9 Ṣugbọn nwọn o ma sin Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn, ẹniti emi o gbe kalẹ fun wọn. 10 Njẹ nisisiyi, má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi; ki o má si fòya, iwọ Israeli: nitorina sa wò o, emi o gbà ọ lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati igbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì yio si dẹruba a. 11 Nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ: bi emi tilẹ ṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi kì yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn, emi kì o jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya. 12 Nitori bayi li Oluwa wi, Ifarapa rẹ jẹ aiwotan, ọgbẹ rẹ si jẹ aijina. 13 Kò si ẹniti o gba ọ̀ran rẹ rò, lati dì i, ọja imularada kò si. 14 Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i, 15 Ẽṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikãnu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ; ẹ̀ṣẹ rẹ si pọ̀ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ. 16 Nitorina gbogbo awọn ti o jẹ ọ, li a o jẹ; ati gbogbo awọn ọta rẹ, olukuluku wọn, ni yio lọ si igbekun: ati awọn ti o kó ọ yio di kikó, ati gbogbo awọn ti o fi ọ ṣe ijẹ li emi o fi fun ijẹ. 17 Nitori emi o fi ọja imularada lè ọ, emi o si wò ọgbẹ rẹ san, li Oluwa wi; nitori nwọn pè ọ li ẹniti a le jade; Sioni, ti ẹnikan kò ṣafẹri rẹ̀! 18 Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o tun mu igbekun agọ Jakobu pada bọ̀; emi o si ṣãnu fun ibugbe rẹ̀; a o si kọ́ ilu na sori okiti rẹ̀, a o si ma gbe ãfin gẹgẹ bi ilana rẹ̀. 19 Ati lati inu wọn ni ọpẹ́ ati ohùn awọn ti nyọ̀ yio ti jade: emi o si mu wọn bi si i, nwọn kì o si jẹ diẹ; emi o ṣe wọn li ogo pẹlu, nwọn kì o si kere. 20 Awọn ọmọ wọn pẹlu yio ri bi ti iṣaju, ijọ wọn li a o fi idi rẹ̀ mulẹ niwaju mi, emi o si jẹ gbogbo awọn ti o ni wọn lara niya. 21 Ọlọla rẹ̀ yio si jẹ lati inu ara wọn wá, alakoso rẹ̀ lati ãrin rẹ̀; emi o si mu u sunmọ tosi, on o si sunmọ ọdọ mi: nitori tani ẹniti o mura ọkàn rẹ̀ lati sunmọ ọdọ mi? li Oluwa wi. 22 Ẹnyin o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin. 23 Wò o, afẹfẹ iji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori oluṣe-buburu. 24 Ibinu kikan Oluwa kì o pada, titi on o fi ṣe e, ati titi on o fi mu èro ọkàn rẹ̀ ṣẹ: li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.

Jeremiah 31

Israẹli Pada sílé

1 LI àkoko na, li Oluwa wi, li emi o jẹ Ọlọrun gbogbo idile Israeli, nwọn o si jẹ enia mi. 2 Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀. 3 Oluwa ti fi ara hàn fun mi lati okere pe, Nitõtọ emi fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa ore-ọfẹ mọ fun ọ. 4 Emi o tun ọ kọ́, iwọ o si di kikọ, iwọ wundia Israeli! iwọ o si fi timbreli rẹ ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ o si jade lọ ni ọwọ́-ijo ti awọn ti nyọ̀. 5 Iwọ o gbìn ọgba-ajara sori oke Samaria: awọn àgbẹ yio gbìn i, nwọn o si jẹ ẹ. 6 Nitori ọjọ na ni eyi, ti awọn oluṣọ lori oke Efraimu yio kigbe pe, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a goke lọ si Sioni sọdọ Oluwa, Ọlọrun wa. 7 Nitori bayi li Oluwa wi; ẹ fi ayọ̀ kọrin didùn fun Jakobu, ẹ si ho niti olori awọn orilẹ-ède: ẹ kede! ẹ yìn, ki ẹ si wipe: Oluwa, gbà awọn enia rẹ la, iyokù Israeli! 8 Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ. 9 Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi. 10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀. 11 Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ. 12 Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara. 13 Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn. 14 Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi.

Àánú OLUWA lórí Israẹli

15 Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si. 16 Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta. 17 Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn. 18 Lõtọ emi ti gbọ́ Efraimu npohùnrere ara rẹ̀ bayi pe; Iwọ ti nà mi, emi si di ninà, bi ọmọ-malu ti a kò kọ́; yi mi pada, emi o si yipada; nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun mi. 19 Lõtọ lẹhin ti emi yipada, mo ronupiwada; ati lẹhin ti a kọ́ mi, mo lu ẹ̀gbẹ mi: oju tì mi, lõtọ, ani mo dãmu, nitoripe emi ru ẹ̀gan igba ewe mi. 20 Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi. 21 Gbe àmi-ọ̀na soke, ṣe ọwọ̀n àmi: gbe ọkàn rẹ si opopo ọ̀na, ani ọ̀na ti iwọ ti lọ: tun yipada, iwọ wundia Israeli, tun yipada si ilu rẹ wọnyi. 22 Iwọ o ti ṣina kiri pẹ to, iwọ apẹhinda ọmọbinrin? nitori Oluwa dá ohun titun ni ilẹ na pe, Obinrin kan yio yi ọkunrin kan ka.

Ọjọ́ Iwájú Àwọn Eniyan Ọlọrun Yóo Dára

23 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́! 24 Juda ati gbogbo ilu rẹ̀ yio ma jumọ gbe inu rẹ̀, agbẹ, ati awọn ti mba agbo-ẹran lọ kakiri, 25 Nitori emi tù ọkàn alãrẹ ninu, emi si ti tẹ gbogbo ọkàn ikãnu lọrun. 26 Lori eyi ni mo ji, mo si wò; õrun mi si dùn mọ mi. 27 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbin ile Israeli ati Judah ni irugbin enia, ati irugbin ẹran. 28 Yio si ṣe, pe gẹgẹ bi emi ti ṣọ́ wọn, lati fà tu, ati lati fa lulẹ, ati lati wo lulẹ, ati lati parun, ati lati pọnloju, bẹ̃ni emi o ṣọ́ wọn, lati kọ́, ati lati gbìn, li Oluwa wi. 29 Li ọjọ wọnni, nwọn kì yio wi mọ pe, Awọn baba ti jẹ eso ajara aipọn, ehín si ti kan awọn ọmọ. 30 Ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori aiṣedede rẹ̀, olukuluku ti o jẹ eso ajara-aipọn ni ehín yio kan. 31 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun. 32 Kì iṣe bi majẹmu na ti emi ba baba wọn dá li ọjọ na ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti nwọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ alakoso wọn sibẹ, li Oluwa wi; 33 Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi. 34 Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi kì o si ranti ẹ̀ṣẹ wọn mọ. 35 Bayi li Oluwa wi ti o fi õrùn fun imọlẹ li ọsan, ilana oṣupa ati irawọ fun imọlẹ li oru, ti o rú okun soke tobẹ̃, ti riru omi rẹ̀ nho; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: 36 Bi ilana wọnyi ba yẹ̀ kuro niwaju mi, li Oluwa wi, njẹ iru-ọmọ Israeli pẹlu yio dẹkun lati ma jẹ orilẹ-ède niwaju mi lailai. 37 Bayi li Oluwa wi, Bi a ba le wọ̀n ọrun loke, ti a si le wá ipilẹ aiye ri nisalẹ, emi pẹlu yio ta iru-ọmọ Israeli nù nitori gbogbo eyiti nwọn ti ṣe, li Oluwa wi. 38 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti a o kọ́ ilu na fun Oluwa lati ile-iṣọ Hananeeli de ẹnu-bode igun odi. 39 Okùn ìwọn yio si nà jade siwaju lẹba rẹ̀ lori oke Garebi, yio si lọ yi Goati ka. 40 Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.

Jeremiah 32

Jeremiah Ra Ilẹ̀

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọdun kẹwa Sedekiah, ọba Juda, eyiti o jẹ ọdun kejidilogun ti Nebukadnessari. 2 Nigbana ni ogun ọba Babeli ha Jerusalemu mọ: a si se Jeremiah woli mọ agbala ile túbu, ti o wà ni ile ọba Juda. 3 Nitori Sedekiah, ọba Judah, ti se e mọ, wipe, Ẽṣe ti iwọ sọtẹlẹ, ti o si wipe, Bayi li Oluwa wi, wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si ko o; 4 Ati Sedekiah, ọba Juda, kì yio bọ́ li ọwọ awọn ara Kaldea, ṣugbọn a o fi i le ọwọ ọba Babeli, Lõtọ, yio si ba a sọ̀rọ li ojukoju, oju rẹ̀ yio si ri oju rẹ̀. 5 On o si mu Sedekiah lọ si Babeli, nibẹ ni yio si wà titi emi o fi bẹ̀ ẹ wò, li Oluwa wi; bi ẹnyin tilẹ ba awọn ará Kaldea jà, ẹnyin kì yio ṣe rere. 6 Jeremiah si wipe, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe, 7 Wò o, Hanameeli, ọmọ Ṣallumu, ẹ̀gbọn rẹ, yio tọ̀ ọ wá, wipe, Iwọ rà oko mi ti o wà ni Anatoti: nitori titọ́ irasilẹ jẹ tirẹ lati rà a. 8 Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa. 9 Emi si rà oko na lọwọ Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ti o wà ni Anatoti, mo si wọ̀n owo fun u, ṣekeli meje ati ìwọn fadaka mẹwa. 10 Mo si kọ ọ sinu iwe, mo si di i, mo si pè awọn ẹlẹri si i, mo si wọ̀n owo na ninu òṣuwọn. 11 Mo si mu iwe rirà na eyiti a dí nipa aṣẹ ati ilana, ati eyiti a ṣi silẹ. 12 Mo si fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, ọmọ Masseiah, li oju Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ati niwaju awọn ẹlẹri ti o kọ orukọ wọn si iwe rirà na, niwaju gbogbo ọkunrin Juda ti o joko ni àgbala ile túbu. 13 Mo si paṣẹ fun Baruki li oju wọn wipe, 14 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wipe, Mu iwe wọnyi, iwe rirà yi, ti a dí, ati iwe yi ti a ṣi silẹ; ki o si fi wọn sinu ikoko, ki nwọn ki o le wà li ọjọ pupọ. 15 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe, A o tun rà ile ati oko ati ọgba-ajara ni ilẹ yi.

Adura Jeremiah

16 Mo si gbadura si Oluwa lẹhin igbati mo ti fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, wipe, 17 A! Oluwa Ọlọrun! wò o, iwọ ti o da ọrun on aiye nipa agbara nla rẹ ati ninà apa rẹ: kò si ohun-kohun ti o ṣoro fun ọ. 18 Iwọ ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun, o si san aiṣedede awọn baba si aiya awọn ọmọ lẹhin wọn: Ọlọrun titobi, Alagbara! Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. 19 Titobi ni igbimọ, ati alagbara ni iṣe; oju rẹ ṣí si gbogbo ọ̀na awọn ọmọ enia: lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀ ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀: 20 Ẹniti o gbe àmi ati iṣẹ-iyanu kalẹ ni Egipti, titi di oni yi, ati lara Israeli, ati lara enia miran: ti iwọ si ti ṣe orukọ fun ara rẹ, gẹgẹ bi o ti ri li oni yi. 21 Ti o si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ agbara, ati ninà apa ati ẹ̀ru nla mu Israeli enia rẹ jade ni ilẹ Egipti. 22 Ti iwọ si ti fun wọn ni ilẹ yi, eyiti iwọ bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn, ilẹ ti nṣàn fun wara ati oyin; 23 Nwọn si wá, nwọn si ni i; ṣugbọn nwọn kò gbà ohùn rẹ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò rìn ninu ofin rẹ, nwọn kò ṣe gbogbo eyiti iwọ paṣẹ fun wọn lati ṣe: iwọ si pè gbogbo ibi yi wá sori wọn: 24 Wo o! odi ọta! nwọn sunmọ ilu lati kó o; a si fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea, ti mba a jà, niwaju idà, ati ìyan, àjakalẹ-àrun: ati ohun ti iwọ ti sọ, ṣẹ; si wò o, iwọ ri i. 25 Ṣugbọn iwọ ti sọ fun mi, Oluwa Ọlọrun! pe, Iwọ fi owo rà oko na fun ara rẹ, ki o si pe awọn ẹlẹri; sibẹ, a o fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea. 26 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá, wipe, 27 Wò o, emi li Oluwa, Ọlọrun gbogbo ẹran-ara: ohun kan ha wà ti o ṣòro fun mi bi? 28 Nitorina, bayi li Oluwa wi, Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, on o si kó o: 29 Ati awọn ara Kaldea, ti mba ilu yi jà, nwọn o wá, nwọn o si tẹ iná bọ̀ ilu yi, nwọn o si kun u, ati ile, lori orule eyiti nwọn ti nrubọ turari si Baali, ti nwọn si ti ndà ẹbọ ohun mimu fun ọlọrun miran, lati mu mi binu. 30 Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda ti ṣe kiki ibi niwaju mi lati igba èwe wọn wá: nitori awọn ọmọ Israeli ti fi kiki iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu, li Oluwa wi. 31 Nitori ilu yi ti jẹ ohun ibinu ati irunu fun mi lati ọjọ ti nwọn ti kọ ọ wá titi di oni yi; tobẹ̃ ti emi o mu u kuro niwaju mi. 32 Nitori gbogbo ibi awọn ọmọ Israeli, ati awọn ọmọ Juda, ti nwọn ti ṣe lati mu mi binu, awọn, awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn, ati awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu. 33 Nwọn si ti yi ẹhin wọn pada si mi, kì isi ṣe oju: emi kọ́ wọn, mo ndide ni kutukutu lati kọ́ wọn, sibẹ nwọn kò fetisilẹ lati gbà ẹkọ. 34 Nwọn si gbe ohun irira wọn ka inu ile na, ti a fi orukọ mi pè, lati sọ ọ di aimọ́. 35 Nwọn si kọ́ ibi giga Baali, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati fi awọn ọmọkunrin wọn ati awọn ọmọbinrin wọn fun Moleki; ti emi kò paṣẹ fun wọn, bẹ̃ni kò wá si ọkàn mi, pe ki nwọn ki o mã ṣe ohun irira yi, lati mu Juda ṣẹ̀.

Ìlérí Ìrètí

36 Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ilu yi, sipa eyiti ẹnyin wipe, A o fi le ọwọ ọba Babeli, nipa idà, ati nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ-arun. 37 Wò o, emi o kó wọn jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi ti le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mã gbe lailewu: 38 Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn. 39 Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọ̀na kan, ki nwọn ki o le bẹ̀ru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn: 40 Emi o si ba wọn dá majẹmu aiyeraiye, pe emi kì o yipada lẹhin wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o fi ibẹ̀ru mi si ọkàn wọn, ti nwọn kì o lọ kuro lọdọ mi. 41 Lõtọ, emi o yọ̀ lori wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o si gbìn wọn si ilẹ yi li otitọ tinutinu mi ati tọkàntọkàn mi. 42 Nitori bayi li Oluwa wi; Gẹgẹ bi emi ti mu gbogbo ibi nla yi wá sori awọn enia yi, bẹ̃ni emi o mu gbogbo rere ti emi ti sọ nipa ti wọn wá sori wọn. 43 Enia o si rà oko ni ilẹ yi, nipa eyi ti ẹnyin wipe, Ahoro ni laisi enia, laisi ẹran, a fi le ọwọ awọn ara Kaldea. 44 Enia yio fi owo rà oko, nwọn o kọ ọ sinu iwe, nwọn o si dí i, nwọn o si pe awọn ẹlẹri ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda, ati ni ilu ọwọ́-oke na, ati ni ilu afonifoji, ati ni ilu iha gusu; nitori emi o mu igbekun wọn pada wá, li Oluwa wi.

Jeremiah 33

Ìlérí Ìrètí Mìíràn

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá lẹ̃keji, nigbati a si se e mọ ninu agbala ile túbu, wipe, 2 Bayi li Oluwa wi, ẹniti o ṣe e, Oluwa, ti o pinnu rẹ̀, lati fi idi rẹ̀ mulẹ; Oluwa li orukọ rẹ̀; 3 Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀. 4 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ile ilu yi, ati niti ile awọn ọba Juda ti a wó lulẹ ati nitori odi ati nitori idà; 5 Nwọn wá lati ba awọn ara Kaldea jà, ṣugbọn lati fi okú enia kún wọn, awọn ẹniti Emi pa ninu ibinu mi ati ninu irunu mi, ati nitori gbogbo buburu wọnni, nitori eyiti emi ti pa oju mi mọ fun ilu yi. 6 Wò o, emi o fi ọjá ati õgùn imularada dì i, emi o si wò wọn san, emi o si fi ọ̀pọlọpọ alafia ati otitọ hàn fun wọn. 7 Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju. 8 Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi. 9 Ilu na yio si jẹ orukọ ayọ̀ fun mi, iyìn ati ọlá niwaju gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye, ti nwọn gbọ́ gbogbo rere ti emi ṣe fun wọn: nwọn o si bẹ̀ru, nwọn o si warìri, nitori gbogbo ore ati nitori gbogbo alafia ti emi ṣe fun u. 10 Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran. 11 Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi. 12 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Papa-oko awọn oluṣọ-agutan yio tun wà, ti nwọn mu ẹran-ọsin dubulẹ ni ibi yi, ti o dahoro, laini enia ati laini ẹran, ati ni gbogbo ilu rẹ̀! 13 Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi. 14 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu ohun rere na, ti emi ti leri fun ilẹ Israeli ati fun ile Juda, ṣẹ. 15 Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, emi o jẹ ki Ẹka ododo ki o hu soke fun Dafidi; ẹniti yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na. 16 Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA. 17 Nitori bayi li Oluwa wi; A kì o fẹ ọkunrin kan kù lọdọ Dafidi lati joko lori itẹ́ ile Israeli lailai. 18 Bẹ̃ni awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, kì yio fẹ ọkunrin kan kù niwaju mi lati ru ẹbọ sisun, ati lati dana ọrẹ ohun jijẹ, ati lati ṣe irubọ lojojumọ. 19 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, wipe, 20 Bayi li Oluwa wi; Bi ẹnyin ba le bà majẹmu mi ti ọsan jẹ, ati majẹmu mi ti oru, tí ọsan ati oru kò le si li akoko wọn; 21 Nigbana ni majẹmu mi pẹlu Dafidi, iranṣẹ mi le bajẹ, pe ki on ki o má le ni ọmọ lati joko lori itẹ rẹ̀; ati pẹlu awọn ọmọ Lefi, awọn alufa, awọn iranṣẹ mi. 22 Gẹgẹ bi a kò ti le ka iye ogun-ọrun, tabi ki a le wọ̀n iyanrin eti okun: bẹ̃ni emi o sọ iru-ọmọ Dafidi iranṣẹ mi di pupọ, ati awọn ọmọ Lefi, ti nṣe iranṣẹ fun mi. 23 Ọ̀rọ Oluwa si tọ Jeremiah wá, wipe, 24 Iwọ kò ha ro eyi ti awọn enia yi ti sọ wipe, Idile meji ti Oluwa ti yàn, o ti kọ̀ wọn silẹ̀? nitorina ni nwọn ti ṣe kẹgan awọn enia mi, pe nwọn kì o le jẹ orilẹ-ède kan mọ li oju wọn. 25 Bayi li Oluwa wi, Bi emi kò ba paṣẹ majẹmu mi ti ọsan ati ti oru, pẹlu ilana ọrun ati aiye, 26 Nigbana ni emi iba ta iru-ọmọ Jakobu nù, ati Dafidi, iranṣẹ mi, ti emi kì o fi mu ninu iru-ọmọ rẹ̀ lati ṣe alakoso lori iru-ọmọ Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu: nitori emi o mu ki igbekun wọn ki o pada bọ̀, emi o si ṣãnu fun wọn.

Jeremiah 34

Iṣẹ́ tí A Rán sí Sedekiah

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, ni wakati ti Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀, ati gbogbo ijọba ilẹ-ijọba ọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn orilẹ-ède, mba Jerusalemu ati gbogbo ilu rẹ̀ ja, wipe: 2 Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi: Lọ, ki o si sọ fun Sedekiah, ọba Juda, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si fi iná kun u: 3 Iwọ kì o si le sala kuro lọwọ rẹ̀, ṣugbọn ni mimú a o mu ọ, a o si fi ọ le e lọwọ; oju rẹ yio si ri oju ọba Babeli, on o si ba ọ sọ̀rọ lojukoju, iwọ o si lọ si Babeli. 4 Sibẹ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, iwọ Sedekiah, ọba Juda: Bayi li Oluwa wi niti rẹ, Iwọ kì yio ti ipa idà kú. 5 Iwọ o kú li alafia: ati bi ijona-isinkú awọn baba rẹ, awọn ọba igbãni ti o wà ṣaju rẹ, bẹ̃ni nwọn o si ṣe ijona-isinkú fun ọ, nwọn o si pohunrere rẹ, pe, Yẽ oluwa! nitori eyi li ọ̀rọ ti emi ti sọ, li Oluwa wi. 6 Jeremiah woli, si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun Sedekiah, ọba Juda ni Jerusalemu. 7 Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi.

Wọ́n Rẹ́ Àwọn Ẹrú Jẹ

8 Ọ̀rọ ti o tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa lẹhin ti Sedekiah, ọba, ti ba gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu dá majẹmu, lati kede omnira fun wọn. 9 Pe, ki olukuluku enia le jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia, iranṣẹbinrin rẹ̀, ti iṣe ọkunrin Heberu tabi obinrin Heberu, lọ lọfẹ; ki ẹnikẹni ki o má mu ara Juda, arakunrin rẹ̀, sìn. 10 Njẹ nigbati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo enia, ti nwọn dá majẹmu yi, gbọ́ pe ki olukuluku ki o jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku, iranṣẹbinrin rẹ̀, lọ lọfẹ, ki ẹnikan má mu wọn sin wọn mọ, nwọn gbọ́, nwọn si jọ̃ wọn lọwọ. 11 Ṣugbọn lẹhin na nwọn yi ọkàn pada, nwọn si mu ki awọn iranṣẹkunrin ati awọn iranṣẹbinrin, awọn ẹniti nwọn ti jẹ ki o lọ lọfẹ, ki o pada, nwọn si mu wọn sin bi iranṣẹkunrin ati bi iranṣẹbinrin. 12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, wipe, 13 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi, pe; Emi ba awọn baba nyin dá majẹmu li ọjọ ti emi mu wọn jade lati ilẹ Egipti, kuro ninu oko-ẹrú, wipe, 14 Li opin ọdọdun meje ki olukuluku enia jẹ ki arakunrin rẹ̀ ki o lọ, ani ara Heberu ti o ta ara rẹ̀ fun ọ; yio si sìn ọ li ọdun mẹfa, nigbana ni iwọ o jẹ ki o lọ lọfẹ lọdọ rẹ: ṣugbọn awọn baba nyin kò gbọ́ temi, bẹ̃ni wọn ko tẹti wọn silẹ. 15 Ẹnyin si yi ọkàn pada loni, ẹ si ti ṣe eyi ti o tọ li oju mi, ni kikede omnira, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀; ẹnyin si ti dá majẹmu niwaju mi ni ile ti a fi orukọ mi pè: 16 Ṣugbọn ẹnyin yipada, ẹ si sọ orukọ mi di ẽri, olukuluku enia si mu ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia iranṣẹbinrin rẹ̀, ti on ti sọ di omnira ni ifẹ wọn, ki o pada, ẹnyin si mu wọn sìn lati jẹ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, fun nyin. 17 Nitorina bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò feti si mi, ni kikede omnira, ẹgbọ́n fun aburo rẹ̀, ati ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀: wò o, emi o kede omnira fun nyin, li Oluwa wi, si idà, si ajakalẹ-àrun, ati si ìyan, emi o si fi nyin fun iwọsi ni gbogbo ijọba ilẹ aiye. 18 Emi o si ṣe awọn ọkunrin na, ti o ti ré majẹmu mi kọja, ti kò ṣe ọ̀rọ majẹmu ti nwọn ti dá niwaju mi, bi ẹgbọrọ malu ti nwọn ti ke meji, ti nwọn si kọja lãrin ipin mejeji rẹ̀, 19 Awọn ijoye Juda, ati awọn ijoye Jerusalemu, awọn ìwẹfa, ati awọn alufa, ati gbogbo enia ilẹ na, ti o kọja lãrin ipin mejeji ẹgbọrọ malu na; 20 Emi o fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: okú wọn yio si jẹ onjẹ fun awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun awọn ẹranko igbẹ. 21 Ati Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀ li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ ogun ọba Babeli, ti o ṣi lọ kuro lọdọ nyin. 22 Wò o, emi o paṣẹ, li Oluwa wi: emi o si mu wọn pada si ilu yi; nwọn o si ba a jà, nwọn o si kó o, nwọn o si fi iná kún u: emi o si ṣe ilu Juda li ahoro laini olugbe.

Jeremiah 35

Jeremiah ati Àwọn Ọmọ Rekabu

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe: 2 Lọ si ile awọn ọmọ Rekabu, ki o si ba wọn sọ̀rọ, ki o si mu wọn wá si ile Oluwa, si ọkan ninu iyara wọnni, ki o si fun wọn li ọti-waini mu. 3 Nigbana ni mo mu Jaasaniah, ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ile awọn ọmọ Rekabu; 4 Mo si mu wọn wá si ile Oluwa, sinu iyara awọn ọmọ Hanani, ọmọ Igdaliah, enia Ọlọrun, ti o wà lẹba iyara awọn ijoye, ti o wà li oke iyara Maaseiah, ọmọ Ṣallumu, olutọju ẹnu-ọ̀na, 5 Mo si gbe ìkoko ti o kún fun ọti-waini pẹlu ago, ka iwaju awọn ọmọ ile Rekabu, mo si wi fun wọn pe: Ẹ mu ọti-waini. 6 Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio mu ọti-waini, nitori Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa, paṣẹ fun wa pe: Ẹnyin kò gbọdọ mu ọti-waini, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin lailai. 7 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ kọ́ ile, tabi ki ẹ fun irugbin, tabi ki ẹ gbin ọgba-àjara, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ni; ṣugbọn ni gbogbo ọjọ nyin li ẹnyin o ma gbe inu agọ; ki ẹnyin ki o le wà li ọjọ pupọ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nṣe atipo. 8 Bayi li awa gbà ohùn Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa gbọ́ ninu gbogbo eyiti o palaṣẹ fun wa, ki a má mu ọti-waini ni gbogbo ọjọ wa, awa, awọn aya wa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa; 9 Ati ki a má kọ ile lati gbe; bẹ̃ni awa kò ni ọgba-ajara, tabi oko, tabi ohùn ọgbin. 10 Ṣugbọn awa ngbe inu agọ, a si gbọran, a si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jonadabu, baba wa, palaṣẹ fun wa. 11 O si ṣe, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli, goke wá si ilẹ na, ni awa wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si Jerusalemu, nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Kaldea, ati nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Siria: bẹ̃ni awa ngbe Jerusalemu. 12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá wipe: 13 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Lọ, ki o si sọ fun awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu pe, Ẹnyin kì yio ha gbà ẹkọ lati feti si ọ̀rọ mi? li Oluwa wi. 14 Ọ̀rọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, ti o pa laṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o má mu ọti-waini, ni a mu ṣẹ; nwọn kò si mu ọti-waini titi di oni yi. Nitoriti nwọn gbọ́ ofin baba wọn, emi si ti nsọ̀rọ fun nyin, emi dide ni kutukutu, emi nsọ: ṣugbọn ẹnyin kò fetisi ti emi. 15 Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi. 16 Lõtọ awọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, pa ofin baba wọn mọ, ti o pa laṣẹ fun wọn; ṣugbọn awọn enia yi kò gbọ́ ti emi: 17 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o mu wá sori Juda, ati sori gbogbo olugbe Jerusalemu, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn; nitori ti emi ti ba wọn sọ̀rọ, nwọn kò si gbọ́; mo si ti pè wọn, nwọn kò si dahùn. 18 Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin: 19 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Jonadabu, ọmọ Rekabu kì yio fẹ ọkunrin kan kù lati duro niwaju mi lailai.

Jeremiah 36

Baruku Ka Àkọsílẹ̀ ninu Ilé OLUWA

1 O si ṣe li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe, 2 Mu iwe-kiká fun ara rẹ̀, ki o si kọ sinu rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ ti emi ti sọ si Israeli, ati si Juda, ati si gbogbo orilẹ-ède, lati ọjọ ti mo ti sọ fun ọ, lati ọjọ Josiah titi di oni yi. 3 O le jẹ pe ile Juda yio gbọ́ gbogbo ibi ti mo pinnu lati ṣe si wọn; ki nwọn ki o le yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀; ki emi ki o dari aiṣedede wọn ati ẹ̀ṣẹ wọn ji wọn. 4 Nigbana ni Jeremiah pè Baruku, ọmọ Neriah; Baruku si kọ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun u, sori iwe-kiká na. 5 Jeremiah si paṣẹ fun Baruku pe, a se mi mọ: emi kò le lọ si ile Oluwa: 6 Nitorina iwọ lọ, ki o si kà ninu iwe-kika na, ti iwọ kọ lati ẹnu mi wá, ọ̀rọ Oluwa li eti awọn enia ni ile Oluwa li ọjọ ãwẹ: ati pẹlu, iwọ o si kà a li eti gbogbo Juda, ti nwọn jade wá lati ilu wọn. 7 O le jẹ pe, ẹ̀bẹ wọn yio wá siwaju Oluwa, nwọn o si yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀: nitoripe nla ni ibinu ati irunu ti Oluwa ti sọ si awọn enia yi. 8 Baruku, ọmọ Neriah, si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jeremiah, woli, ti palaṣẹ fun u, lati ka ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe ni ile Oluwa. 9 O si ṣe li ọdun karun Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, li oṣu kẹsan ni nwọn kede ãwẹ niwaju Oluwa, fun gbogbo enia ni Jerusalemu: ati fun gbogbo awọn enia ti o wá lati ilu Juda, si Jerusalemu. 10 Baruku si ka ọ̀rọ Jeremiah lati inu iwe ni ile Oluwa, ni iyara Gemariah, ọmọ Ṣafani, akọwe, ni àgbala oke, nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa li eti gbogbo enia.

Wọ́n ka Àkọsílẹ̀ náà sí Etígbọ̀ọ́ Àwọn Ìjòyè

11 Nigbati Mikaiah, ọmọ Gemariah, ọmọ Ṣafani, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe na wá, 12 O si sọkalẹ lọ si ile ọba, sinu iyara akọwe, si wò o, gbogbo awọn ijoye joko nibẹ, Eliṣama, akọwe, ati Delaiah, ọmọ Semaiah, ati Elnatani, ọmọ Akbori, ati Gemariah, ọmọ Safani, ati Sedekiah, ọmọ Hananiah, ati gbogbo awọn ijoye. 13 Nigbana ni Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ wọnni ti o ti gbọ́, fun wọn, nigbati Baruku kà lati inu iwe na li eti awọn enia. 14 Nigbana ni gbogbo awọn ìjoye rán Jehudu, ọmọ Netaniah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Kuṣi, si Baruku wipe, Mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ, lati inu eyiti iwọ kà li eti awọn enia, ki o si wá. Nigbana ni Baruku, ọmọ Neriah, mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ̀, o si wá si ọdọ wọn. 15 Nwọn si wi fun u pe, Joko nisisiyi, ki o si kà a li eti wa. Baruku si kà a li eti wọn. 16 Njẹ, o si ṣe, nigbati nwọn gbọ́ gbogbo ọ̀rọ na, nwọn warìri, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀, nwọn si wi fun Baruku pe, Awa kò le ṣe aisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun ọba. 17 Nwọn si bi Baruku wipe, Sọ fun wa nisisiyi, bawo ni iwọ ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi lati ẹnu rẹ̀? 18 Baruku si da wọn lohùn pe; Lati ẹnu rẹ̀ li o si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun mi, emi si fi tadawa kọ wọn sinu iwe na. 19 Nigbana ni awọn ijoye sọ fun Baruku pe, Lọ, fi ara rẹ pamọ, iwọ ati Jeremiah; má si jẹ ki ẹnikan mọ̀ ibi ti ẹnyin wà.

Ọba Sun Ìwé Àkọsílẹ̀ Náà Níná

20 Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba. 21 Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba. 22 Ọba si ngbe ile igba-otutu li oṣu kẹsan: ina si njo niwaju rẹ̀ ninu idana. 23 O si ṣe, nigbati Jehudu ti kà ewe mẹta tabi mẹrin, ọba fi ọbẹ ke iwe na, o si sọ ọ sinu iná ti o wà ninu idaná, titi gbogbo iwe-kiká na fi joná ninu iná ti o wà lori idaná. 24 Sibẹ nwọn kò warìri, nwọn kò si fa aṣọ wọn ya, ani ọba, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi. 25 Ṣugbọn Elnatani ati Delaiah ati Gemariah bẹbẹ lọdọ ọba ki o máṣe fi iwe-kiká na joná, kò si fẹ igbọ́ ti wọn. 26 Ṣugbọn ọba paṣẹ fun Jerameeli, ọmọ Hameleki, ati Seraiah, ọmọ Asraeli, ati Ṣelemiah, ọmọ Abdeeli, lati mu Baruku akọwe, ati Jeremiah woli: ṣugbọn Oluwa fi wọn pamọ.

Jeremiah kọ Ìwé Mìíràn

27 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá, lẹhin ti ọba ti fi iwe-kiká na ati ọ̀rọ ti Baruku kọ lati ẹnu Jeremiah wá joná, wipe, 28 Tun mu iwe kiká miran, ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ iṣaju sinu rẹ̀ ti o wà ninu iwe-kiká ekini, ti Jehoiakimu, ọba Juda, ti fi joná. 29 Iwọ o si sọ niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti fi iwe-kiká yi joná o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi kọwe sinu rẹ̀, pe: Lõtọ ọba Babeli yio wá yio si pa ilẹ yi run, yio si pa enia ati ẹran run kuro ninu rẹ̀? 30 Nitorina bayi li Oluwa wi niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, On kì yio ni ẹniti yio joko lori itẹ Dafidi: a o si sọ okú rẹ̀ nù fun oru li ọsan, ati fun otutu li õru. 31 Emi o si jẹ on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ niya, nitori aiṣedede wọn; emi o si mu wá sori wọn, ati sori awọn olugbe Jerusalemu, ati sori awọn ọkunrin Juda, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn, ṣugbọn nwọn kò gbọ́. 32 Nigbana ni Jeremiah mu iwe-kiká miran, o si fi i fun Baruku, akọwe, ọmọ Neriah; ẹniti o kọwe sinu rẹ̀ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ iwe ti Jehoiakimu, ọba Juda ti sun ninu iná: a si fi ọ̀rọ pupọ bi iru eyi kún ọ̀rọ iwe na pẹlu.

Jeremiah 37

Ohun Tí Sedekiah Bèèrè lọ́wọ́ Jeremiah

1 SEDEKIAH, ọmọ Josiah si jọba ni ipo Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ẹniti Nebukadnessari, ọba Babeli, fi jẹ ọba ni ilẹ Juda. 2 Ṣugbọn ati on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia ilẹ na, kò fetisi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa Jeremiah, woli. 3 Sedekiah, ọba si ran Jehukali, ọmọ Ṣelemiah, ati Ṣefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, si Jeremiah woli, wipe: Njẹ, bẹbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun wa fun wa. 4 Jeremiah si nwọle o si njade lãrin awọn enia: nitori nwọn kò ti ifi i sinu tubu. 5 Ogun Farao si jade lati Egipti wá: nigbati awọn ara Kaldea ti o dótì Jerusalemu si gbọ́ iró wọn, nwọn lọ kuro ni Jerusalemu. 6 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah, woli wá, wipe, 7 Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi pe, Bayi li ẹnyin o sọ fun ọba Juda, ti o rán nyin si mi, lati bere lọwọ mi: Wò o, ogun Farao ti o jade lati ràn nyin lọwọ, yio pada si ilẹ rẹ̀, ani Egipti. 8 Awọn ara Kaldea yio si tun wá, nwọn o si ba ilu yi jà, nwọn o kó o, nwọn o si fi iná kún u. 9 Bayi li Oluwa wi; Ẹ máṣe tan ọkàn nyin jẹ, wipe, Ni lilọ awọn ara Kaldea yio lọ kuro lọdọ wa: nitoriti nwọn kì yio lọ. 10 Nitori bi o tilẹ jẹ pe, ẹnyin lu gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti mba nyin jà bolẹ, ti o si jẹ pe awọn ọkunrin ti o gbọgbẹ li o kù ninu wọn: sibẹ nwọn o dide, olukuluku ninu agọ rẹ̀, nwọn o si fi iná kun ilu yi.

Wọ́n Mú Jeremiah, Wọ́n sì Tì Í Mọ́lé

11 O si ṣe, nigbati ogun awọn ara Kaldea goke lọ kuro ni Jerusalemu nitori ogun Farao, 12 Ni Jeremiah jade kuro ni Jerusalemu lati lọ si ilẹ Benjamini lati pin ini lãrin awọn enia. 13 Nigbati o si wà li ẹnu-bode Benjamini, balogun iṣọ kan wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Irijah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Hananiah; on si mu Jeremiah woli, wipe, Iwọ nsa tọ̀ awọn ara Kaldea lọ. 14 Jeremiah si wipe: Eke! emi kò sa tọ awọn ara Kaldea lọ. Ṣugbọn kò gbọ́ tirẹ̀: bẹ̃ni Irijah mu Jeremiah, o si mu u tọ̀ awọn ijoye wá. 15 Nitorina ni awọn ijoye ṣe binu si Jeremiah, nwọn si lù u, nwọn si fi sinu tubu ni ile Jonatani, akọwe; nitori nwọn ti fi eyi ṣe ile túbu. 16 Bẹ̃ni Jeremiah lọ inu ile-túbu ati inu iyara ṣiṣokunkun. Jeremiah si wà nibẹ li ọjọ pupọ; 17 Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli. 18 Pẹlupẹlu Jeremiah sọ fun Sedekiah, ọba, pe; Ẹṣẹ wo ni mo ṣẹ̀ ọ, tabi awọn iranṣẹ rẹ, tabi awọn enia yi, ti ẹnyin fi mi sinu ile-túbu? 19 Nibo ni awọn woli nyin ha wà nisisiyi, awọn ti nsọtẹlẹ fun nyin, wipe, Ọba Babeli kì yio wá sọdọ nyin ati si ilẹ yi? 20 Nitorina gbọ́ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀bẹ mi, emi bẹ̀ ọ, ki o wá si iwaju rẹ; ki iwọ ki o má jẹ ki emi pada si ile Jonatani akọwe, ki emi má ba kú nibẹ. 21 Sedekiah, ọba, si paṣẹ pe ki nwọn ki o fi Jeremiah pamọ sinu agbala ile-túbu, ati pe ki nwọn ki o ma fun u ni iṣu akara kọ̃kan lojojumọ, lati ita awọn alakara, titi gbogbo akara fi tan ni ilu. Jeremiah si wà li agbala ile-túbu.

Jeremiah 38

Wọ́n Ju Jeremiah sinu Kànga Gbígbẹ

1 NIGBANA ni Ṣefatiah, ọmọ Mattani, ati Gedaliah, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemiah, ati Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ ti Jeremiah ti sọ fun gbogbo enia, wipe, 2 Bayi li Oluwa wi pe, ẹniti o ba joko ni ilu yi yio kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-àrun, ẹniti o ba si jade tọ̀ awọn ara Kaldea lọ yio yè; a o si fi ẹmi rẹ́ fun u bi ikogun, yio si yè. 3 Bayi li Oluwa wi pe, lõtọ a o fi ilu yi le ọwọ ogun ọba Babeli, ẹniti yio si kó o. 4 Awọn ijoye si sọ fun ọba pe, Jẹ ki a pa ọkunrin yi: nitori bayi li o mu ọwọ awọn ologun ti o kù ni ilu yi rọ, pẹlu ọwọ gbogbo enia, ni sisọ iru ọ̀rọ bayi fun wọn: nitori ọkunrin yi kò wá alafia awọn enia yi, bikoṣe ibi wọn. 5 Sedekiah ọba, si wipe, Wò o, on wà li ọwọ nyin, nitori ọba kò le iṣe ohun kan lẹhin nyin. 6 Nwọn si mu Jeremiah, nwọn si sọ ọ sinu iho Malkiah ọmọ Hammeleki, ti o wà li agbala ile-túbu: nwọn fi okun sọ Jeremiah kalẹ sisalẹ. Omi kò si si ninu iho na, bikoṣe ẹrẹ̀: Jeremiah si rì sinu ẹrẹ̀ na. 7 Nigbati Ebedmeleki, ara Etiopia, iwẹfa kan, ti o wà ni ile ọba, gbọ́ pe, nwọn fi Jeremiah sinu iho: ọba joko nigbana li ẹnu-bode Benjamini; 8 Ebedmeleki si jade lati ile ọba lọ, o si sọ fun ọba wipe, 9 Oluwa mi, ọba! awọn ọkunrin wọnyi ti ṣe ibi ni gbogbo eyi ti nwọn ti ṣe si Jeremiah woli pe, nwọn ti sọ ọ sinu iho; ebi yio si fẹrẹ pa a kú ni ibi ti o gbe wà: nitori onjẹ kò si mọ ni ilu. 10 Nigbana ni ọba paṣẹ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe, Mu ọgbọ̀n enia lọwọ lati ihin lọ, ki o si fà Jeremiah soke lati inu iho, ki o to kú. 11 Ebedmeleki si mu awọn enia na pẹlu rẹ̀, o si lọ si ile ọba labẹ iyara iṣura, o si mu akisa ati oṣuka lati ibẹ wá, o si fi okùn sọ̀ wọn kalẹ si Jeremiah ninu iho. 12 Ebedmeleki, ara Etiopia, si sọ fun Jeremiah pe, Fi akisa ati oṣuka wọnyi si abẹ abia rẹ, lori okùn. Jeremiah si ṣe bẹ̃. 13 Bẹ̃ni nwọn fi okùn fà Jeremiah soke, nwọn si mu u goke lati inu iho wá: Jeremiah si wà ni agbala ile-tubu.

Sedekiah Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Jeremiah

14 Nigbana ni Sedekiah, ọba, ranṣẹ, o mu Jeremiah woli, wá sọdọ rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na kẹta ti o wà ni ile Oluwa: ọba si wi fun Jeremiah pe, Emi o bi ọ lere ohun kan: máṣe fi nkankan pamọ fun mi. 15 Jeremiah si wi fun Sedekiah pe, Bi emi ba sọ fun ọ, iwọ kì o ha pa mi nitõtọ? bi mo ba si fi imọran fun ọ, iwọ kì yio fetisi ti emi. 16 Sedekiah, ọba, si bura nikọkọ fun Jeremiah, wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹni ti o da ẹmi wa yi, emi kì yio pa ọ, bẹ̃ni emi kì yio fi ọ le ọwọ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwá ẹmi rẹ. 17 Nigbana ni Jeremiah sọ fun Sedekiah pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe: Bi iwọ o ba jade nitõtọ tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni ọkàn rẹ yio yè, a ki yio si fi iná kun ilu yi; iwọ o si yè ati ile rẹ. 18 Ṣugbọn bi iwọ kì yio ba jade tọ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni a o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, nwọn o si fi iná kun u, iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn. 19 Sedekiah ọba, si sọ fun Jeremiah pe, Ẹ̀ru awọn ara Juda ti o ya tọ awọn ara Kaldea mbà mi, ki nwọn ki o má ba fi mi le wọn lọwọ; nwọn a si fi mi ṣẹsin. 20 Ṣugbọn Jeremiah wipe, nwọn kì yio si fi ọ le wọn lọwọ, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa ti mo sọ fun ọ: yio si dara fun ọ, ọkàn rẹ yio si yè. 21 Ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ lati jade lọ, eyi li ohun ti Oluwa ti fi hàn mi: 22 Si wò o, gbogbo awọn obinrin ti o kù ni ile ọba Juda li a o mu tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, awọn obinrin wọnyi yio si wipe, Awọn ọrẹ rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si ti bori rẹ: ẹsẹ rẹ̀ rì sinu ẹrẹ̀ wayi, nwọn pa ẹhin dà. 23 Nwọn o si mu gbogbo awọn aya rẹ ati awọn ọmọ rẹ jade tọ awọn ara Kaldea lọ: iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn, ọwọ ọba Babeli yio si mu ọ: iwọ o si mu ki nwọn ki o fi iná kun ilu yi. 24 Sedekiah si wi fun Jeremiah pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ niti ọ̀rọ wọnyi, ki iwọ má ba kú. 25 Ṣugbọn bi awọn ijoye ba gbọ́ pe emi ti ba ọ sọ̀rọ, bi nwọn ba si wá sọdọ rẹ, ti nwọn sọ fun ọ pe, Sọ fun wa nisisiyi eyi ti iwọ ti sọ fun ọba, máṣe fi pamọ fun wa, awa kì o si pa ọ; ati eyi ti ọba sọ fun ọ pẹlu: 26 Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Emi mu ẹ̀bẹ mi wá siwaju ọba, pe ki o má mu mi pada lọ si ile Jonatani, lati kú sibẹ. 27 Gbogbo awọn ijoye si tọ̀ Jeremiah wá, nwọn bi i lere: o si sọ fun wọn gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti ọba ti palaṣẹ fun u. Bẹ̃ni nwọn dakẹ nwọn si jọ̃rẹ̀; nitori ẹnikan kò gbọ́ ọ̀ran na. 28 Jeremiah si ngbe agbala ile-túbu titi di ọjọ ti a kó Jerusalemu.

Jeremiah 39

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 O si ṣe, nigbati a kó Jerusalemu (li ọdun kẹsan Sedekiah, ọba Juda, li oṣu kẹwa ni Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀ wá si Jerusalemu, nwọn si dó tì i. 2 Ati li ọdun kọkanla Sedekiah, li oṣu kẹrin, li ọjọ keṣan oṣu li a fọ ilu na.) 3 Gbogbo awọn ijoye ọba Babeli si wọle, nwọn si joko li ẹnu-bode ãrin, ani Nergali-Ṣareseri, Samgari-nebo, Sarsikimu, olori iwẹfa, Nergali-Ṣareseri, olori amoye, pẹlu gbogbo awọn ijoye ọba Babeli iyokù. 4 O si ṣe, nigbati Sedekiah, ọba Juda, ati gbogbo awọn ologun ri wọn, nigbana ni nwọn sá, nwọn si jade kuro ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ọgbà ọba ati ẹnu-bode lãrin odi mejeji, nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ. 5 Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa wọn, nwọn si ba Sedekiah, ọba, ni pẹtẹlẹ Jeriko; nigbati nwọn si mu u, nwọn mu u goke wá sọdọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Ribla ni ilẹ Hamati, nibiti o sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀. 6 Nigbana ni ọba Babeli pa awọn ọmọ Sedekiah ni Ribla, niwaju rẹ̀; ọba Babeli si pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu. 7 Pẹlupẹlu o fọ Sedekiah li oju, o si fi ẹ̀wọn dè e, lati mu u lọ si Babeli. 8 Awọn ara Kaldea si fi ile ọba ati ile awọn enia joná, nwọn si wó odi Jerusalemu lulẹ. 9 Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ti ya lọ, ti o ya sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn enia iyokù ti o kù. 10 Ṣugbọn Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu diẹ ninu awọn enia, ani awọn talaka ti kò ni nkan rara, joko ni ilẹ Juda, o si fi ọgba-àjara ati oko fun wọn li àkoko na.

Wọ́n Dá Jeremiah Sílẹ̀

11 Nebukadnessari, ọba Babeli, si paṣẹ fun Nebusaradani, balogun iṣọ, niti Jeremiah, wipe, 12 Mu u, ki o si bojuto o, má si ṣe e ni ibi kan; ṣugbọn gẹgẹ bi on ba ti sọ fun ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe fun u. 13 Bẹ̃ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ati Nebuṣaṣbani, olori iwẹfa, ati Nergali Ṣareseri, olori amoye, ati gbogbo ijoye ọba Babeli, si ranṣẹ, 14 Ani nwọn ranṣẹ nwọn si mu Jeremiah jade ni àgbala ile-tubu, nwọn si fi fun Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, pe ki o mu u lọ si ile: bẹ̃ni o ngbe ãrin awọn enia.

Ìrètí Wà fún Ebedmeleki

15 Ọrọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, nigbati a se e mọ ninu àgbala ile-túbu, wipe, 16 Lọ, ki o si sọ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o mu ọ̀rọ mi wá sori ilu yi fun ibi, kì isi ṣe fun rere; nwọn o si ṣẹ niwaju rẹ li ọjọ na. 17 Ṣugbọn emi o gbà ọ li ọjọ na, li Oluwa wi: a kì o si fi ọ le ọwọ awọn enia na ti iwọ bẹ̀ru. 18 Nitori emi o gbà ọ là nitõtọ, iwọ kì o si ti ipa idà ṣubu, ṣugbọn ẹ̀mi rẹ yio jẹ bi ikogun fun ọ: nitoripe iwọ ti gbẹkẹ rẹ le mi, li Oluwa wi.

Jeremiah 40

Jeremiah Ń Gbé Ọ̀dọ̀ Gedalaya

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, lẹhin ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti ranṣẹ pè e lati Rama. Nitori nigbati o mu u, a fi ẹwọn dè e lãrin gbogbo awọn igbekun Jerusalemu ati Juda, ti a kó ni ìgbekun lọ si Babeli. 2 Balogun iṣọ si mu Jeremiah, o si wi fun u pe, Oluwa, Ọlọrun rẹ, ti sọ ibi yi si ilu yi. 3 Oluwa si ti mu u wá, o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi: nitoripe ẹnyin ti ṣẹ̀ si Oluwa, ẹ kò si gbọ́ ohùn rẹ̀, nitorina ni nkan yi ṣe de ba nyin. 4 Njẹ nisisiyi, wò o, mo tú ọ silẹ li oni kuro ninu ẹ̀wọn ti o wà li ọwọ rẹ: bi o ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, kalọ, emi o boju to ọ: ṣugbọn bi kò ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, jọwọ rẹ̀; wò o, gbogbo ilẹ li o wà niwaju rẹ, ibi ti o ba dara ti o ba si tọ li oju rẹ lati lọ, lọ sibẹ. 5 Bi bẹ̃kọ, pada tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilu Juda, ki o si mã ba a gbe lãrin ọpọ enia, tabi ibikibi ti o ba tọ li oju rẹ, lati lọ, lọ sibẹ̀. Balogun iṣọ si fun u li onjẹ ati ẹbun; o si jọ́wọ́ rẹ̀ lọwọ. 6 Jeremiah si lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ni Mispa; o si mba a gbe lãrin awọn enia, ti o kù ni ilẹ na.

Gedalaya, Gomina Juda

7 Njẹ nigbati gbogbo awọn olori ogun, ti o wà li oko, awọn ati awọn ọkunrin wọn, gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, jẹ bãlẹ ni ilẹ na, o si ti fi awọn ọkunrin fun u, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati ninu awọn talaka ilẹ na, ninu awọn ti a kò kó lọ ni igbekun si Babeli. 8 Nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati Johanani, ati Jonatani, awọn ọmọ Karea, ati Seraiah, ọmọ Tanhumeti, ati awọn ọmọ Efai, ara Netofa, ati Jesaniah, ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn, 9 Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, si bura fun wọn ati fun awọn ọkunrin wọn, wipe: Ẹ má bẹ̀ru lati sìn awọn ara Kaldea: ẹ gbe ilẹ̀ na, ki ẹ si mã sin ọba Babeli, yio si dara fun nyin. 10 Bi o ṣe ti emi, wò o, emi o ma gbe Mispa, lati sìn awọn ara Kaldea, ti yio tọ wa wá; ṣugbọn ẹnyin ẹ kó ọti-waini jọ, ati eso-igi, ati ororo, ki ẹ si fi sinu ohun-elo nyin, ki ẹ si gbe inu ilu nyin ti ẹnyin ti gbà. 11 Pẹlupẹlu gbogbo awọn ara Juda, ti o wà ni Moabu, ati lãrin awọn ọmọ Ammoni, ati ni Edomu, ati awọn ti o wà ni gbogbo ilẹ wọnni gbọ́ pe, ọba Babeli ti fi iyokù silẹ fun Juda, ati pe o ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣolori wọn; 12 Gbogbo awọn ara Juda si pada lati ibi gbogbo wá ni ibi ti a ti lé wọn si, nwọn si wá si ilẹ Juda sọdọ Gedaliah si Mispa, nwọn si kó ọti-waini ati eso igi jọ pupọpupọ.

Wọ́n Pa Gedalaya

13 Ṣugbọn Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà li oko, tọ̀ Gedaliah wá si Mispa. 14 Nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ dajudaju pe: Baalisi, ọba awọn ọmọ Ammoni, ti ran Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati pa ọ? Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, kò gbà wọn gbọ́. 15 Nigbana ni Johanani, ọmọ Karea, si sọ nikọkọ fun Gedaliah ni Mispa pe, Jẹ ki emi lọ, mo bẹ ọ, emi o si pa Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ẹnikan kì yio si mọ̀: Ẽṣe ti on o fi pa ọ, ti gbogbo awọn ara Juda ti a kojọ tì ọ, yio tuka, ati iyokù Juda yio ṣegbe? 16 Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, sọ fun Johanani, ọmọ Karea pe, Iwọ kò gbọdọ ṣe nkan yi, nitori eke ni iwọ ṣe mọ Iṣmaeli.

Jeremiah 41

1 O si ṣe li oṣu keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, ninu iru-ọmọ ọba, ati awọn ijoye ọba, ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, nwọn tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, wá ni Mispa: nibẹ ni nwọn jumọ jẹun ni Mispa. 2 Nigbana ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati awọn ọkunrin mẹwa ti nwọn wà pẹlu rẹ̀, nwọn fi idà kọlu Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, nwọn si pa a, on ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilẹ na. 3 Pẹlupẹlu Iṣmaeli pa gbogbo awọn ara Juda ti o wà pẹlu rẹ̀, ani pẹlu Gedaliah, ni Mispa, ati awọn ara Kaldea, ti a ri nibẹ, awọn ologun. 4 O si ṣe li ọjọ keji lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ti ẹnikan kò si mọ̀. 5 Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa. 6 Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si jade lati Mispa lọ ipade wọn, bi o ti nlọ, o nsọkun: o si ṣe, bi o ti pade wọn, o wi fun wọn pe, jẹ ki a lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu. 7 O si ṣe, nigbati nwọn de ãrin ilu, ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, pa wọn, on, ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀ si sọ wọn sinu iho. 8 Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn. 9 Ati iho na ninu eyi ti Iṣmaeli ti sọ gbogbo okú ọkunrin wọnyi si, awọn ti o ti pa pẹlu Gedaliah, ni eyiti Asa, ọba, ti ṣe nitori ibẹ̀ru Baaṣa, ọba Israeli: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si fi awọn ti a pa kún u. 10 Iṣmaeli si kó gbogbo iyokù awọn enia ti o wà ni Mispa ni igbekun, awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti o kù ni Mispa, awọn ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti fi le Gedaliah, ọmọ Ahikamu lọwọ: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si kó wọn ni igbekun, o si kuro nibẹ lati rekọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni. 11 Ṣugbọn nigbati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o pẹlu rẹ̀, gbọ́ ibi ti Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ti ṣe, 12 Nigbana ni nwọn kó gbogbo awọn ọkunrin, nwọn si lọ iba Iṣmaeli, ọmọ Netaniah jà, nwọn si ri i li ẹba omi nla ti o wà ni Gibeoni. 13 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu Iṣmaeli ri Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o pẹlu rẹ̀, nwọn si yọ̀, 14 Bẹ̃ni gbogbo awọn enia, ti Iṣmaeli ti kó lọ ni igbekun lati Mispa, yi oju wọn, nwọn si yipada, nwọn si lọ sọdọ Johanani, ọmọ Karea. 15 Ṣugbọn Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, bọ́ lọwọ Johanani pẹlu ọkunrin mẹjọ, o si lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni. 16 Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, si mu gbogbo iyokù awọn enia ti o ti gbà lọwọ Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati Mispa, lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ani, akọni ọkunrin ogun, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn iwẹfa, awọn ti o ti tun mu pada lati Gibeoni wá: 17 Nwọn si kuro nibẹ, nwọn si joko ni ibugbe Kinhamu, ti o wà lẹba Betlehemu, lati lọ ide Egipti. 18 Nitoriti ẹ̀ru ba wọn niwaju awọn ara Kaldea, nitoriti Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ẹniti ọba Babeli fi jẹ bãlẹ ni ilẹ na.

Jeremiah 42

Àwọn Eniyan náà Ní kí Jeremiah Gbadura fún Àwọn

1 NIGBANA ni gbogbo awọn olori ogun, ati Johanani, ọmọ Karea, ati Jesaniah, ọmọ Hoṣaiah, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere de ẹni-nla, nwọn wá, 2 Nwọn si sọ fun Jeremiah woli, pe, Awa bẹ ọ, jẹ ki ẹ̀bẹ wa ki o wá siwaju rẹ, ki o si gbadura fun wa si Oluwa Ọlọrun rẹ, ani fun gbogbo iyokù yi; (nitori lati inu ọ̀pọlọpọ, diẹ li awa kù, gẹgẹ bi oju rẹ ti ri wa:) 3 Ki Oluwa Ọlọrun rẹ le fi ọ̀na hàn wa ninu eyi ti awa iba rìn, ati ohun ti awa iba ṣe. 4 Jeremiah, woli, si wi fun wọn pe, emi gbọ́; wò o, emi o gbadura si Oluwa Ọlọrun nyin gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin; yio si ṣe, pe ohunkohun ti Oluwa yio fi da nyin lohùn emi o sọ ọ fun nyin; emi kì o ṣẹ nkankan kù fun nyin. 5 Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa. 6 Iba ṣe rere, iba ṣe ibi, awa o gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, sọdọ ẹniti awa rán ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.

Ìdáhùn OLUWA sí Adura Jeremiah

7 O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá. 8 Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla. 9 O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀; 10 Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin. 11 Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀. 12 Emi o si fi ãnu hàn fun nyin, ki on ki o le ṣãnu fun nyin, ki o si mu ki ẹnyin pada si ilẹ nyin. 13 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, Awa kì yio gbe ilẹ yi, ti ẹnyin kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́. 14 Wipe, bẹ̃kọ̀; ṣugbọn awa fẹ lọ si ilẹ Egipti, nibiti awa kì yio ri ogun-kogun, ti a kì o si gbọ́ iró fère, ti ebi onjẹ kò ni ipa wa, nibẹ li awa o si mã gbe: 15 Njẹ nisisiyi, nitorina, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin iyokù Juda, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Bi ẹ ba gbe oju nyin patapata le ati lọ si Egipti, bi ẹnyin ba lọ lati ṣe atipo nibẹ, 16 Yio si ṣe, idà ti ẹnyin bẹ̀ru, yio si le nyin ba ni ilẹ Egipti; ati ìyan, ti ẹnyin bẹ̀ru, yio tẹle nyin girigiri nibẹ ni Egipti; nibẹ li ẹnyin o si kú. 17 Bẹ̃ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn gbe oju wọn si ati lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ; nwọn o kú, nipa idà, nipa ìyan, tabi nipa àjakalẹ-arun, ẹnikẹni ninu wọn kì yio kù, tabi kì o sala kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori wọn. 18 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Gẹgẹ bi emi ti dà ibinu mi ati irunu mi sori awọn olugbe Jerusalemu; bẹ̃ni emi o dà irunu mi le nyin lori, ẹnyin ti yio lọ si Egipti: ẹnyin o si di ẹni-ègun, ati ẹni-iyanu, ati ẹ̀gan, ati ẹ̀sin; ẹnyin kì yio si tun ri ibi yi mọ. 19 Oluwa ti sọ niti nyin, ẹnyin iyokù Juda, ẹ má lọ si Egipti: ẹ mọ̀ dajudaju pe emi ti jẹri si nyin li oni yi. 20 Nitori ọkàn nyin li ẹnyin tanjẹ, nigbati ẹnyin rán mi si Oluwa, Ọlọrun nyin, wipe, Gbadura fun wa si Oluwa, Ọlọrun wa: ati gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Oluwa Ọlọrun wa yio wi, bẹ̃ni ki o sọ fun wa, awa o si ṣe e. 21 Emi si ti sọ fun nyin loni; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn Oluwa, Ọlọrun nyin, ati gbogbo eyi ti on ti ran mi si nyin. 22 Njẹ nitorina, ẹ mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin o kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun, ni ibẹ na nibiti ẹnyin fẹ lati lọ iṣe atipo.

Jeremiah 43

Wọ́n Mú Jeremiah Lọ sí Ijipti

1 O si ṣe, nigbati Jeremiah pari ọ̀rọ isọ fun gbogbo awọn enia, ani gbogbo ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun wọn, eyiti Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a si wọn, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi. 2 Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ: 3 Ṣugbọn Baruku, ọmọ Neriah, li o fi ọ̀rọ si ọ li ẹnu si wa, nitori lati fi wa le awọn ara Kaldea lọwọ, lati pa wa ati lati kó wa ni igbekun lọ si Babeli. 4 Bẹ̃ni Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, ati gbogbo awọn enia, kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, lati má gbe ilẹ Juda, 5 Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, si mu gbogbo iyokù Juda, ti nwọn pada lati gbogbo orilẹ-ède wá, ni ibi ti a ti le wọn si, lati ma gbe ilẹ Juda; 6 Awọn ọkunrin, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti kù silẹ lọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremiah woli, ati Baruku, ọmọ Neriah, 7 Nwọn si wá si ilẹ Egipti: nitori nwọn kò gbà ohùn Oluwa gbọ́: bayi ni nwọn wá si Tafanesi. 8 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá ni Tafanesi, wipe, 9 Mu okuta nla li ọwọ rẹ ki o si fi wọn pamọ sinu amọ̀, ni ile-iná briki ti o wà ni ẹnu-ọ̀na ile Farao ni Tafanesi, li oju awọn ọkunrin Juda. 10 Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, pe, wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu Nebukadnessari, ọba Babeli, iranṣẹ mi, emi o si gbe itẹ rẹ̀ kalẹ lori okuta wọnyi, ti emi ti fi pamọ; on o si tẹ itẹ ọla rẹ̀ lori wọn. 11 Nigbati o ba si de, on o kọlu ilẹ Egipti, on o si fi ti ikú, fun ikú: ti igbekun, fun igbekun; ati ti idà, fun idà. 12 Emi o si dá iná kan ni ile awọn oriṣa Egipti; on o si sun wọn, yio si kó wọn lọ; on o si fi ilẹ Egipti wọ ara rẹ̀ laṣọ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iwọ̀ aṣọ rẹ̀; yio si jade lati ibẹ lọ li alafia. 13 Yio si fọ́ ere ile-õrùn, ti o wà ni ilẹ Egipti tũtu, yio si fi iná kun ile awọn oriṣa awọn ara Egipti.

Jeremiah 44

Wọ́n Pa Gedalaya

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá fun gbogbo awọn ara Juda ti ngbe ilẹ Egipti, ti ngbe Migdoli, ati Tafanesi, ati Nofu, ati ilẹ Patrosi, wipe, 2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, ẹnyin ti ri gbogbo ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ati sori gbogbo ilu Juda; si wò o, ahoro ni nwọn li oni yi, ẹnikan kò si gbe inu wọn. 3 Nitori ìwa-buburu wọn ti nwọn ti hú lati mu mi binu, ni lilọ lati sun turari ati lati sìn awọn ọlọrun miran, ti nwọn kò mọ̀, awọn, tabi ẹnyin, tabi awọn baba nyin. 4 Emi si ran gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, emi dide ni kutukutu, mo rán wọn, wipe, A! ẹ máṣe ohun irira yi ti emi korira. 5 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ lati yipada kuro ninu ìwa-buburu wọn, ki nwọn ki o má sun turari fun ọlọrun miran. 6 Nitorina ni mo ṣe dà ìrunu mi ati ibinu mi jade, a si daná rẹ̀ ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nwọn si di ofo ati ahoro, gẹgẹ bi ti oni yi. 7 Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, nitori kini ẹ ṣe da ẹ̀ṣẹ nla yi si ọkàn nyin, lati ke ninu nyin ani ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati ọmọ-ọmu, kuro lãrin Juda, lati má kù iyokú fun nyin; 8 Ninu eyiti ẹnyin fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, ni sisun turari fun ọlọrun miran ni ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin lọ lati ṣatipo, ki ẹ le ke ara nyin kuro, ati ki ẹ le jẹ ẹni-ègun ati ẹsin, lãrin gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye? 9 Ẹnyin ha ti gbagbe ìwa-buburu awọn baba nyin, ati ìwa-buburu awọn ọba Juda, ati ìwa-buburu awọn aya wọn, ati ìwa-buburu ẹnyin tikara nyin, ati ìwa-buburu awọn aya nyin, ti nwọn ti hù ni ilẹ Juda, ati ni ita Jerusalemu. 10 Nwọn kò rẹ̀ ara wọn silẹ titi di oni yi, bẹ̃ni wọn kò bẹ̀ru, tabi ki nwọn ki o rìn ninu ofin mi, tabi ninu ilana mi ti emi gbe kalẹ niwaju nyin ati niwaju awọn baba nyin. 11 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, wò o emi doju mi kọ nyin fun ibi, ati lati ke gbogbo Juda kuro. 12 Emi o si mu gbogbo iyokù Juda, ti o ti gbe oju wọn si ati lọ si ilẹ Egipti, lati ṣatipo nibẹ, gbogbo wọn ni yio si run, nwọn o si ṣubu ni ilẹ Egipti; nwọn o si run nipa idà ati nipa ìyan, nwọn o kú lati ẹni-kekere wọn titi de ẹni-nla wọn, nipa idà, ati nipa ìyan: nwọn o si di ẹni-ègun, ẹni-iyanu, ati ẹni-ẹ̀gan, ati ẹsin. 13 Nitori emi o bẹ̀ awọn ti ngbe Egipti wò, gẹgẹ bi emi ti jẹ Jerusalemu niya, nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun; 14 Kì o si si ẹniti o sala, ati ẹniti o kù, fun awọn iyokù Juda, ti o wọ ilẹ Egipti lati ma ṣatipo nibẹ, ti yio pada si ilẹ Juda, si eyiti nwọn ni ifẹ ati pada lọ igbe ibẹ: nitori kò si ọkan ti yio pada bikoṣe iru awọn ti o sala. 15 Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn mọ̀ daju pe, awọn aya wọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ati gbogbo awọn obinrin ti o duro nibẹ, apejọ nla, ati gbogbo awọn enia ti ngbe ilẹ Egipti ani ni Patrosi, da Jeremiah lohùn, wipe, 16 Ọ̀rọ ti iwọ sọ fun wa li orukọ Oluwa, awa kì yio feti si tirẹ. 17 Ṣugbọn dajudaju awa o ṣe ohunkohun ti o jade lati ẹnu wa wá, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, gẹgẹ bi awa ti ṣe, awa, ati awọn baba wa, awọn ọba wa, ati awọn ijoye wa ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nigbana awa ni onjẹ pupọ, a si ṣe rere, a kò si ri ibi. 18 Ṣugbọn lati igba ti awa ti fi sisun turari fun ayaba ọrun silẹ, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, awa ti ṣalaini ohun gbogbo, a si run nipa idà ati nipa ìyan. 19 Ati nigbati awa sun turari fun ayaba ọrun ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u, lẹhin awọn ọkọ wa ni awa ha dín akara didùn rẹ̀ lati bọ ọ, ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u bi? 20 Nigbana ni Jeremiah sọ fun gbogbo awọn enia, fun awọn ọkunrin, ati fun awọn obinrin, ati fun gbogbo awọn enia ti o ti fun u li èsi yi wipe. 21 Turari ti ẹnyin sun ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu, ẹnyin ati awọn baba nyin, awọn ọba nyin, ati awọn ijoye nyin, ati awọn enia ilẹ na, Oluwa kò ha ranti rẹ̀, kò ha si wá si ọkàn rẹ̀? 22 Tobẹ̃ ti Oluwa kò le rọju pẹ mọ, nitori buburu iṣe nyin, ati nitori ohun irira ti ẹnyin ti ṣe; bẹ̃ni ilẹ nyin di ahoro, ati iyanu ati ègun, laini olugbe, bi o ti ri li oni yi. 23 Nitori ti ẹnyin ti sun turari, ati nitori ti ẹnyin ṣẹ̀ si Oluwa, ti ẹnyin kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, ti ẹ kò rin ninu ofin rẹ̀, ati ninu ilana rẹ̀, ati ninu ọ̀rọ ẹri rẹ̀; nitorina ni ibi yi ṣe de si nyin, bi o ti ri li oni yi. 24 Jeremiah sọ pẹlu fun gbogbo awọn enia, ati fun gbogbo awọn obinrin na pe, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa gbogbo Juda ti o wà ni ilẹ Egipti: 25 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli sọ, wipe, Ẹnyin ati awọn aya nyin, ẹnyin fi ẹnu nyin sọ̀rọ, ẹ si fi ọwọ nyin mu ṣẹ, ẹ si wipe, lõtọ awa o san ẹ̀jẹ́ wa ti awa ti jẹ, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, njẹ ni pipamọ, ẹ pa ẹ̀jẹ́ nyin mọ, ati ni sisan ẹ san ẹ̀jẹ́ nyin. 26 Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo Juda ti ngbe ilẹ Egipti, sa wò o, emi ti fi orukọ nlanla mi bura, li Oluwa wi, pé, a kì yio pè orukọ mi li ẹnu ọkunrin-kunrin Juda ni gbogbo ilẹ Egipti, wipe, Oluwa, Ọlọrun wà. 27 Wò o, emi o ṣọ wọn fun ibi, kì si iṣe fun rere: ati gbogbo awọn ọkunrin Juda ti o wà ni ilẹ Egipti ni a o run nipa idà, ati nipa ìyan, titi nwọn o fi tan. 28 Ati awọn ti o sala lọwọ idà, yio pada ni iye diẹ lati ilẹ Egipti si ilẹ Juda; ati gbogbo iyokù Juda, ti o lọ si ilẹ Egipti lati ṣatipo nibẹ, yio mọ̀ ọ̀rọ tani yio duro, temi, tabi ti wọn. 29 Eyi ni yio si jẹ àmi fun nyin, li Oluwa wi, pe, emi o jẹ nyin niya ni ibiyi, ki ẹnyin le mọ̀ pe: ọ̀rọ mi yio duro dajudaju si nyin fun ibi: 30 Bayi li Oluwa wi; wò o, emi o fi Farao-hofra, ọba Egipti, le ọwọ awọn ọta rẹ̀, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi rẹ̀; gẹgẹ bi emi ti fi Sedekiah, ọba Juda, le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli ọta rẹ̀, ti o si wá ẹmi rẹ̀.

Jeremiah 45

Ìlérí Ọlọrun fún Baruku

1 Ọ̀RỌ ti Jeremiah, woli, sọ fun Baruku, ọmọ Neriah nigbati o ti kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwe tan li ẹnu Jeremiah li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe, 2 Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi fun ọ, iwọ Baruku; 3 Iwọ wipe, Egbé ni fun mi nisisiyi! nitori ti Oluwa ti fi ibanujẹ kún ikãnu mi; ãrẹ̀ mu mi ninu ẹ̀dun mi, emi kò si ri isimi. 4 Bayi ni ki iwọ sọ fun u, Oluwa wi bayi; pe, Wò o, eyi ti emi ti kọ́, li emi o wo lulẹ, ati eyi ti emi ti gbìn li emi o fà tu, ani gbogbo ilẹ yi. 5 Iwọ ha si mbere ohun nla fun ara rẹ? máṣe bere: nitori, wò o, emi o mu ibi wá sori gbogbo ẹran-ara, li Oluwa wi: ṣugbọn ẹmi rẹ li emi o fi fun ọ bi ikogun ni gbogbo ibiti iwọ ba lọ si.

Jeremiah 46

Nebukadinesari ṣẹgun Ijipti ní Kakemiṣi

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah, woli wá si awọn orilẹ-ède. 2 Si Egipti, si ogun Farao-Neko, ọba Egipti, ti o wà lẹba odò Ferate ni iha Karkemiṣi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kọlu ni ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda. 3 Ẹ mura apata ati asà, ẹ si sunmọ tosi si oju ìja, 4 Ẹ di ẹṣin ni gãrì; ẹ gùn wọn, ẹnyin ẹlẹṣin, ẹ duro lẹsẹsẹ ninu akoro nyin; ẹ dan ọ̀kọ, ẹ wọ ẹwu irin. 5 Ẽṣe ti emi ti ri wọn ni ibẹ̀ru ati ni ipẹhinda? awọn alagbara wọn li a lù bolẹ, nwọn sa, nwọn kò si wò ẹhin: ẹ̀ru yika kiri, li Oluwa wi. 6 Ẹni ti o yara, kì yio salọ, alagbara ọkunrin kì yio si sala: ni iha ariwa lẹba odò Ferate ni nwọn o kọsẹ̀, nwọn o si ṣubu. 7 Tani eyi ti o goke wá bi odò, ti omi rẹ̀ nrú gẹgẹ bi odò wọnni? 8 Egipti dide bi odò Nile, omi rẹ̀ si nrú bi omi odò wọnni; o si wipe, Emi o goke lọ, emi o si bò ilẹ aiye, emi o si pa ilu ati awọn olugbe inu rẹ̀ run! 9 Ẹ goke wá, ẹnyin ẹṣin, ẹ si sare kikan, ẹnyin kẹ̀kẹ; ki awọn alagbara si jade wá; awọn ara Etiopia, ati awọn ara Libia, ti o ndi asà mu; ati awọn ara Lidia ti nmu ti o nfa ọrun. 10 Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate. 11 Goke lọ si Gileadi, ki o si mu ikunra, iwọ wundia, ọmọbinrin Egipti: li asan ni iwọ o lò ọ̀pọlọpọ õgùn; ọja-imularada kò si fun ọ. 12 Awọn orilẹ-ède ti gbọ́ itiju rẹ, igbe rẹ si ti kún ilẹ na: nitori alagbara ọkunrin ti kọsẹ lara alagbara, ati awọn mejeji si jumọ ṣubu pọ̀.

Bíbọ̀ Nebukadinesari

13 Ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun Jeremiah, woli, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli wá lati kọlu ilẹ Egipti. 14 Ẹ sọ ọ ni Egipti, ki ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Migdoli, ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Nofu ati Tafanesi: ẹ wipe, duro lẹsẹsẹ, ki o si mura, nitori idà njẹrun yi ọ kakiri. 15 Ẽṣe ti a fi gbá awọn akọni rẹ lọ? nwọn kò duro, nitori Oluwa le wọn. 16 A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara. 17 Nwọn kigbe nibẹ; Farao, ọba Egipti ti ṣegbe: on ti kọja akoko ti a dá! 18 Bi emi ti wà, li Ọba, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, nitõtọ gẹgẹ bi Tabori lãrin awọn oke, ati gẹgẹ bi Karmeli lẹba okun, bẹ̃ni on o de. 19 Iwọ, ọmọbinrin ti ngbe Egipti, pèse ohun-èlo ìrin-ajo fun ara rẹ: nitori Nofu yio di ahoro, a o si fi joná, laini olugbe. 20 Ẹgbọrọ malu ti o dara pupọ ni Egipti, lõtọ, iparun de, o de lati ariwa! 21 Awọn ologun rẹ̀ ti a fi owo bẹ̀, dabi akọmalu abọpa lãrin rẹ̀; awọn wọnyi pẹlu yi ẹhin pada; nwọn jumọ sa lọ pọ: nwọn kò duro, nitoripe ọjọ wàhala wọn de sori wọn, àkoko ibẹwo wọn. 22 Ohùn inu rẹ̀ yio lọ gẹgẹ bi ti ejo; nitori nwọn o lọ pẹlu agbara; pẹlu àkeke lọwọ ni nwọn tọ̀ ọ wá bi awọn akégi. 23 Nwọn o ke igbo rẹ̀ lulẹ, li Oluwa wi, nitori ti a kò le ridi rẹ̀; nitoripe nwọn pọ̀ jù ẹlẹnga lọ, nwọn si jẹ ainiye. 24 Oju yio tì ọmọbinrin Egipti; a o fi i le ọwọ awọn enia ariwa. 25 Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe; Wò o, emi o bẹ̀ Amoni ti No, ati Farao, ati Egipti wò, pẹlu awọn ọlọla wọn, ati awọn ọba wọn; ani Farao ati gbogbo awọn ti o gbẹkẹ le e: 26 Emi o si fi wọn le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati le ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀: lẹhin na, a o si mã gbe inu rẹ̀, gẹgẹ bi ìgba atijọ, li Oluwa wi.

OLUWA Yóo Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

27 Ṣugbọn iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, má si fòya, iwọ Israeli: nitori, wo o, emi o gbà ọ là lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati ilẹ ìgbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì o si dẹ̀ru bà a. 28 Iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu rẹ; nitori emi o ṣe opin patapata ni gbogbo awọn orilẹ-ède, nibiti emi ti le ọ si: ṣugbọn emi kì o ṣe ọ li opin patapata, ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn; sibẹ emi kì yio jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.

Jeremiah 47

Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah woli wá, si awọn ara Filistia, ki Farao ki o to kọlu Gasa. 2 Bayi li Oluwa wi; Wò o, omi dide lati ariwa, yio si jẹ kikun omi akunya, yio si ya bo ilẹ na, ati gbogbo ẹkún inu rẹ̀; ilu na, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀: nigbana ni awọn enia yio kigbe, gbogbo awọn olugbe ilẹ na yio si hu. 3 Nipa ariwo titẹlẹ Patakò ẹsẹ alagbara ẹṣin rẹ̀, nipa iró nla kẹ̀kẹ rẹ̀, ati nipa ariwo nla ayika kẹ̀kẹ rẹ̀; awọn baba kì yio bojuwo ẹhin wò awọn ọmọ wọn nitori ọwọ́ rirọ; 4 Nitori ọjọ na ti mbọ lati pa gbogbo awọn ara Filistia run, ati lati ke gbogbo oluranlọwọ ti o kù kuro lọdọ Tire ati Sidoni: nitori Oluwa yio ṣe ikogun awọn ara Filistia, ani iyokù erekuṣu Kaftori. 5 Ipári de si Gasa, Aṣkeloni ti dahoro, pẹlu iyokù afonifoji wọn: iwọ o ti ṣa ara rẹ lọgbẹ pẹ to? 6 Ye! iwọ idà Oluwa, yio ti pẹ to ki iwọ ki o to gbe jẹ? tẹ ara rẹ bọ inu akọ rẹ, simi! ki o si dakẹ! 7 Ṣugbọn bawo li o ti ṣe le gbe jẹ, nigbati Oluwa ti paṣẹ fun u si Aṣkeloni, ati si ebute okun, nibẹ li o ti ran a lọ!

Jeremiah 48

Ìparun Moabu

1 SI Moabu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Egbe ni fun Nebo! nitoriti a fi ṣe ijẹ: oju tì Kiriataimu, a si kó o: oju tì Misgabu, o si wariri. 2 Ogo Moabu kò si mọ: nwọn ti gbero ibi si i ni Heṣboni pe, wá, ki ẹ si jẹ ki a ke e kuro lati jẹ orilẹ-ède. A o ke ọ lulẹ pẹlu iwọ Madmeni; idà yio tẹle ọ. 3 Ohùn igbe lati Horonaimu, iparun ati idahoro nla! 4 A pa Moabu run; awọn ọmọde rẹ̀ mu ki a gbọ́ igbe. 5 Nitori ẹkun tẹle ẹkun ni ọ̀na igoke lọ si Luhiti: nitori ni ọ̀na isọkalẹ Horonaimu a gbọ́ imi-ẹ̀dun, igbe iparun, pe: 6 Ẹ sa, ẹ gbà ẹmi nyin là, ki ẹ si dabi alaini li aginju! 7 Njẹ nitoriti iwọ ti gbẹkẹle iṣẹ ọwọ rẹ ati le iṣura rẹ, a o si kó iwọ pẹlu: Kemoṣi yio si jumọ lọ si ìgbekun, pẹlu awọn alufa rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀. 8 Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi. 9 Fi iyẹ fun Moabu, ki o ba le fò ki o si lọ, ilu rẹ̀ yio si di ahoro, laisi ẹnikan lati gbe inu rẹ̀. 10 Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ Oluwa ni imẹlẹ, ifibu si li ẹniti o dá idà rẹ̀ duro kuro ninu ẹjẹ.

A pa Àwọn Ìlú Moabu Run

11 Moabu ti wà ni irọra lati igba ewe rẹ̀ wá, o si ti silẹ lori gẹdẹgẹdẹ̀ bi ọtiwaini, a kò si ti dà a lati inu ohun-elo, de ohun-elo bẹ̃ni kò ti ilọ si igbekun: nitorina itọwò rẹ̀ wà ninu rẹ̀, õrun rẹ̀ kò si pada. 12 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o rán awọn atẹni-sapakan si i, ti o si tẹ̀ ẹ sapakan, nwọn o si sọ gbogbo ohun-elo rẹ̀ di ofo, nwọn o si fọ ìgo wọn. 13 Moabu yio si tiju nitori Kemoṣi, gẹgẹ bi ile Israeli ti tiju nitori Beteli, igbẹkẹle wọn. 14 Ẹnyin ha ṣe wipe, akọni ọkunrin ni awa, alagbara fun ogun? 15 A fi Moabu ṣe ijẹ, ẽfin ilu rẹ̀ si goke lọ, awọn àṣayan ọdọmọkunrin rẹ̀ si sure lọ si ibi pipa, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun. 16 Wahala Moabu sunmọ tosi lati de, ipọnju rẹ̀ si nyara kánkan. 17 Gbogbo ẹnyin ti o wà yi i ka, ẹ kedaro rẹ̀; ati gbogbo ẹnyin ti o mọ̀ orukọ rẹ̀, ẹ wipe, bawo li ọpa agbara rẹ fi ṣẹ́, ọpa ogo! 18 Iwọ olugbe ọmọbinrin Diboni, sọkalẹ lati inu ogo, ki o si ma gbe ibi ongbẹ; nitori afiniṣe-ijẹ. Moabu yio goke wá sori rẹ, yio si pa ilu olodi rẹ run. 19 Iwọ olugbe Aroeri! duro lẹba ọ̀na, ki o si wò; bere lọwọ ẹniti nsa, ati ẹniti nsala, wipe, Kili o ṣe? 20 Oju tì Moabu: nitori a wó o lulẹ: ẹ hu, ki ẹ si kigbe; ẹ kede rẹ̀ ni Arnoni pe: a fi Moabu ṣe ijẹ, 21 Idajọ si ti de sori ilẹ pẹtẹlẹ; sori Holoni, ati sori Jahasi, ati sori Mefaati, 22 Ati sori Diboni, ati sori Nebo, ati sori Bet-diblataimu. 23 Ati sori Kiriataimu, ati sori Bet-Gamuli, ati sori Bet-Meoni, 24 Ati sori Kerioti, ati sori Bosra, ati sori gbogbo ilu ilẹ Moabu, lokere ati nitosi. 25 A ke iwo Moabu kuro, a si ṣẹ́ apá rẹ̀, li Oluwa wi.

A Óo Rẹ Moabu sílẹ̀

26 Ẹ mu u yo bi ọmuti: nitori o gberaga si Oluwa: Moabu yio si ma pàfọ ninu ẽbi rẹ̀; on pẹlu yio si di ẹni-ẹ̀gan. 27 Kò ha ri bẹ̃ pe: Israeli jẹ ẹni ẹlẹyà fun ọ bi? bi ẹnipe a ri i lãrin awọn ole? nitori ni igbakũgba ti iwọ ba nsọ̀rọ rẹ̀, iwọ a ma mì ori rẹ. 28 Ẹnyin olugbe Moabu! ẹ fi ilu wọnni silẹ, ki ẹ si mã gbe inu apata, ki ẹ si jẹ gẹgẹ bi oriri ti o kọ́ itẹ rẹ̀ li ẹba ẹnu ihò. 29 Awa ti gbọ́ igberaga Moabu, o gberaga pupọ, iṣefefe rẹ̀, ati afojudi rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati giga ọkàn rẹ̀. 30 Emi mọ̀ ìwa igberaga rẹ̀; li Oluwa wi: ṣugbọn kò ri bẹ̃; ọ̀rọ asan rẹ̀, ti kò le ṣe nkankan. 31 Nitorina ni emi o hu fun Moabu, emi o si kigbe soke fun gbogbo Moabu, lori awọn ọkunrin Kirheresi li a o ṣọ̀fọ. 32 Emi o sọkun fun àjara Sibma jù ẹkùn Jaseri lọ: ẹka rẹ ti rekọja okun lọ, nwọn de okun Jaseri: afiniṣe-ijẹ yio kọlu ikore eso rẹ ati ikore eso-àjara rẹ. 33 Ati ayọ̀ ati ariwo inu-didùn li a mu kuro li oko, ati kuro ni ilẹ Moabu; emi si ti mu ki ọti-waini tán ninu ifunti: ẹnikan kì o fi ariwo tẹ̀ ọti-waini; ariwo ikore kì yio jẹ ariwo ikore mọ. 34 Lati igbe Heṣboni de Eleale, de Jahasi, ni nwọn fọ ohùn wọn, lati Soari de Horonaimu, ti iṣe ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta, nitori omi Nimrimu pẹlu yio dahoro. 35 Emi o si mu ki o dopin ni Moabu, li Oluwa wi: ẹniti o nrubọ ni ibi giga, ati ẹniti nsun turari fun oriṣa rẹ̀. 36 Nitorina ni ọkàn mi ró fun Moabu bi fère, ọkàn mi yio si ró bi fere fun awọn ọkunrin Kirheresi: nitori iṣura ti o kojọ ṣegbe. 37 Nitori gbogbo ori ni yio pá, ati gbogbo irungbọn li a o ke kù: ọgbẹ yio wà ni gbogbo ọwọ, ati aṣọ-ọ̀fọ ni ẹgbẹ mejeji. 38 Ẹkún nlanla ni yio wà lori gbogbo orule Moabu, ati ni ita rẹ̀: nitori emi ti fọ́ Moabu bi ati ifọ́ ohun-elo, ti kò wù ni, li Oluwa wi. 39 Ẹ hu, pe, bawo li a ti wo o lulẹ! bawo ni Moabu ti fi itiju yi ẹhin pada! bẹ̃ni Moabu yio di ẹ̀gan ati idãmu si gbogbo awọn ti o yi i kakiri.

Moabu Kò ní Lè Sá Àsálà

40 Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, on o fò gẹgẹ bi idi, yio si nà iyẹ rẹ̀ lori Moabu. 41 A kó Kerioti, a si kó awọn ilu olodi, ati ọkàn awọn akọni Moabu li ọjọ na yio dabi ọkàn obinrin ninu irọbi rẹ̀. 42 A o si pa Moabu run lati má jẹ orilẹ-ède, nitoripe o ti gberaga si Oluwa. 43 Ẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati okùn-didẹ, yio wà lori rẹ iwọ olugbe Moabu, li Oluwa wi. 44 Ẹniti o ba sa fun ẹ̀ru yio ṣubu sinu ọ̀fin; ati ẹniti o ba jade kuro ninu ọ̀fin ni a o mu ninu okùn-didẹ: nitori emi o mu wá sori rẹ̀, ani sori Moabu, ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi. 45 Awọn ti o sá, duro li aini agbara labẹ ojiji Heṣboni: ṣugbọn iná yio jade wá lati Heṣboni, ati ọwọ-iná lati ãrin Sihoni, yio si jẹ ilẹ Moabu run, ati agbari awọn ọmọ ahoro. 46 Egbe ni fun ọ, iwọ Moabu! orilẹ-ède Kemoṣi ṣegbe: nitori a kó awọn ọkunrin rẹ ni igbekun, ati awọn ọmọbinrin rẹ ni igbekun. 47 Sibẹ emi o tun mu igbekun Moabu pada li ọjọ ikẹhin, li Oluwa wi. Titi de ihin ni idajọ Moabu.

Jeremiah 49

Ìdájọ́ OLUWA Lórí Amoni

1 SI awọn ọmọ Ammoni. Bayi li Oluwa wi; Israeli kò ha ni awọn ọmọkunrin? kò ha ni arole bi? nitori kini Malkomu ṣe jogun Gadi, ti awọn enia rẹ̀ si joko ni ilu rẹ̀? 2 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o mu ki a gbọ́ idagiri ogun ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni: yio si di okiti ahoro, a o si fi iná sun awọn ọmọbinrin rẹ̀; nigbana ni Israeli yio jẹ arole awọn ti o ti jẹ arole rẹ̀, li Oluwa wi. 3 Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀. 4 Ẽṣe ti iwọ fi nṣogo ninu afonifoji, afonifoji rẹ nṣan lọ, iwọ ọmọbinrin ti o gbẹkẹle iṣura rẹ, pe, tani yio tọ̀ mi wá? 5 Wò o, emi o mu ẹ̀ru wá sori rẹ, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, lati ọdọ gbogbo awọn wọnni ti o wà yi ọ kakiri; a o si le nyin, olukuluku enia tàra niwaju rẹ̀; ẹnikan kì o si kó awọn ti nsalọ jọ. 6 Ati nikẹhin emi o tun mu igbekun awọn ọmọ Ammoni pada, li Oluwa wi.

Ìdájọ́ OLUWA lórí Edomu

7 Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi? 8 Ẹ sa, ẹ yipada, ẹ ṣe ibi jijin lati ma gbe ẹnyin olugbe Dedani; nitori emi o mu wahala Esau wá sori rẹ̀, àkoko ti emi o bẹ̀ ẹ wò. 9 Bi awọn aka-eso ba tọ̀ ọ wá, nwọn kì o ha kù ẽṣẹ́ eso ajara silẹ? bi awọn ole ba wá li oru, nwọn kì o ha parun titi yio fi tẹ́ wọn lọrùn. 10 Nitori emi ti tú Esau ni ihoho, emi ti fi ibi ikọkọ rẹ̀ han, on kì o si le fi ara rẹ̀ pamọ; iru-ọmọ rẹ̀ di ijẹ, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn aladugbo rẹ̀, nwọn kò sí mọ́. 11 Fi awọn ọmọ alainibaba rẹ silẹ, emi o si pa wọn mọ lãye; ati ki awọn opó rẹ ki o gbẹkẹle mi. 12 Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, awọn ẹniti kò jẹbi, lati mu ninu ago, ni yio mu u lõtọ: iwọ o ha si lọ li alaijiya? iwọ kì yio lọ li alaijiya, nitori lõtọ iwọ o mu u. 13 Nitori emi ti fi ara mi bura, li Oluwa wi pe: Bosra yio di ahoro, ẹ̀gan, idahoro, ati egún; ati gbogbo ilu rẹ̀ ni yio di ahoro lailai. 14 Ni gbigbọ́ emi ti gbọ́ iró lati ọdọ Oluwa wá, a si ran ikọ̀ si awọn orilẹ-ède pe, ẹ kó ara nyin jọ, ẹ wá sori rẹ̀, ẹ si dide lati jagun. 15 Nitori, wò o, emi o ṣe ọ ni ẹni-kekere lãrin awọn orilẹ-ède, ẹni-ẹgan lãrin awọn enia. 16 Ibanilẹ̀ru rẹ ti tan ọ jẹ, igberaga ọkàn rẹ, nitori iwọ ngbe palapala okuta, ti o joko li ori oke, bi iwọ tilẹ kọ́ itẹ́ rẹ ga gẹgẹ bi idì, sibẹ emi o mu ọ sọkalẹ lati ibẹ wá, li Oluwa wi. 17 Edomu yio si di ahoro: olukuluku ẹniti o ba rekọja rẹ̀, yio dãmu, yio si rẹrin si gbogbo ipọnju rẹ̀. 18 Gẹgẹ bi ni ibiṣubu Sodomu ati Gomorra ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; ẹnikan kì yio gbe ibẹ mọ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀. 19 Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi? 20 Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa ti o ti gbà si Edomu; ati èro rẹ̀ ti o ti gba si awọn olugbe Temani pe, Lõtọ awọn ẹniti o kere julọ ninu agbo-ẹran yio wọ́ wọn kiri, lõtọ nwọn o sọ buka wọn di ahoro lori wọn. 21 Ilẹ o mì nipa ariwo iṣubu wọn, ariwo! a gbọ́ ohùn igbe rẹ̀ li Okun-pupa. 22 Wò o, yio goke wá yio si fò gẹgẹ bi idì, yio si nà iyẹ rẹ̀ sori Bosra: ati li ọjọ na ni ọkàn awọn alagbara ọkunrin Edomu yio dabi ọkàn obinrin ni irọbi.

Ìdájọ́ OLUWA lórí Damasku

23 Si Damasku. Oju tì Hamati, ati Arpadi: nitori nwọn ti gbọ́ ìhin buburu: aiya ja wọn; idãmu wà lẹba okun; nwọn kò le ri isimi. 24 Damasku di alailera, o yi ara rẹ̀ pada lati sa, iwarìri si dì i mu: ẹ̀dun ati irora ti dì i mu, gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi. 25 Bawo ni a kò ṣe fi ilu iyìn silẹ, ilu ayọ̀ mi! 26 Nitorina awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ọkunrin ogun ni a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 27 Emi o si da iná ni odi Damasku, yio si jo ãfin Benhadadi run.

A Óo Rẹ Moabu sílẹ̀

28 Si Kedari, ati si ijọba Hasori, ti Nebukadnessari ọba Babeli, kó: Bayi li Oluwa wi; Dide, goke lọ si Kedari, ki ẹ si pa awọn ọkunrin ìla-õrùn run. 29 Agọ wọn ati agbo-ẹran wọn ni nwọn o kó lọ: nwọn o mu aṣọ agọ wọn fun ara wọn, ati gbogbo ohun-èlo wọn, ati ibakasiẹ wọn; nwọn o si kigbe sori wọn pe, Ẹ̀ru yikakiri! 30 Sa, yara salọ, fi ara pamọ si ibi jijìn, ẹnyin olugbe Hasori, li Oluwa wi; nitori Nebukadnessari ọba Babeli, ti gbìmọ kan si nyin, o si ti gba èro kan si nyin. 31 Dide, goke lọ sọdọ orilẹ-ède kan ti o wà ni irọra, ti o ngbe li ailewu, li Oluwa wi, ti kò ni ilẹkun ẹnu-bode tabi ikere; ti ngbe fun ara rẹ̀. 32 Ibakasiẹ wọn yio si di ikogun, ati ọ̀pọlọpọ ẹran-ọ̀sin wọn yio di ijẹ: emi o si tú awọn ti nda òṣu ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ; emi o si mu wahala wọn de lati iha gbogbo, li Oluwa wi. 33 Hasori yio di ibugbe fun ọ̀wawa, ahoro titi lai: kì o si ẹnikan ti yio joko nibẹ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.

Ìdájọ́ OLUWA lórí Elamu

34 Ọ̀rọ Oluwa ti o tọ Jeremiah, woli, wá si Elamu, ni ibẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, wipe: 35 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o ṣẹ́ ọrun Elamu, ti iṣe olori agbara wọn. 36 Ati sori Elamu ni emi o mu afẹfẹ mẹrin lati igun mẹrẹrin ọrun wá, emi o si tú wọn ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ wọnni, kì o si sí orilẹ-ède kan, nibiti awọn ãsá Elamu kì yio de. 37 Nitori emi o mu Elamu warìri niwaju awọn ọta wọn, ati niwaju awọn ti nwá ẹmi wọn: emi o si mu ibi wá sori wọn, ani ibinu gbigbona mi, li Oluwa wi; emi o si rán idà tẹle wọn, titi emi o fi run wọn. 38 Emi o si gbe itẹ mi kalẹ ni Elamu, emi o si pa ọba ati awọn ijoye run kuro nibẹ, li Oluwa wi. 39 Ṣugbọn yio si ṣe, ni ikẹhin ọjọ, emi o tun mu igbèkun Elamu pada, li Oluwa wi.

Jeremiah 50

1 Ọ̀RỌ ti Oluwa sọ si Babeli ati si ilẹ awọn ara Kaldea nipa ẹnu Jeremiah woli.

Ogun kó Babiloni

2 Ẹ sọ ọ lãrin awọn orilẹ-ède, ẹ si kede, ki ẹ si gbe asia soke: ẹ kede, ẹ má si ṣe bò o: wipe, a kó Babeli, oju tì Beli, a fọ Merodaki tutu; oju tì awọn ere rẹ̀, a fọ awọn òriṣa rẹ̀ tutu. 3 Nitori lati ariwa ni orilẹ-ède kan ti wá sori rẹ̀, ti yio sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ẹnikan kì o gbe inu rẹ̀: nwọn o sa, nwọn o lọ, ati enia ati ẹranko.

Ìpadàbọ̀ Àwọn Ọmọ Israẹli

4 Li ọjọ wọnni ati li àkoko na, li Oluwa wi, awọn ọmọ Israeli yio jumọ wá, awọn, ati awọn ọmọ Juda, nwọn o ma lọ tẹkúntẹkún: nwọn o lọ, nwọn o si ṣafẹri Oluwa Ọlọrun wọn. 5 Nwọn o ma bère ọ̀na Sioni, oju wọn yio si yi sibẹ, nwọn o wá, nwọn o darapọ mọ Oluwa ni majẹmu aiyeraiye, ti a kì yio gbagbe. 6 Awọn enia mi ti jẹ agbo-agutan ti o sọnu: awọn oluṣọ-agutan wọn ti jẹ ki nwọn ṣina, nwọn ti jẹ ki nwọn rìn kiri lori oke: nwọn ti lọ lati ori oke nla de oke kekere, nwọn ti gbagbe ibusun wọn. 7 Gbogbo awọn ti o ri wọn, ti pa wọn jẹ: awọn ọta wọn si wipe, Awa kò jẹbi, nitoripe nwọn ti ṣẹ̀ si Oluwa ibugbe ododo, ati ireti awọn baba wọn, ani Oluwa. 8 Ẹ salọ kuro li ãrin Babeli, ẹ si jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, ki ẹ si jẹ bi obukọ niwaju agbo-ẹran. 9 Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan. 10 Kaldea yio si di ikogun: gbogbo awọn ti o fi ṣe ikogun ni a o tẹ́ lọrùn, li Oluwa wi.

Ìṣubú Babiloni

11 Nitoripe inu nyin dùn, nitoripe ẹnyin yọ̀, ẹnyin olè ti o ji ini mi, nitori ti ẹnyin fi ayọ̀ fò bi ẹgbọrọ malu si koriko tutu, ẹ si nyán bi akọ-ẹṣin: 12 Oju yio tì iya nyin pupọpupọ; itiju yio bo ẹniti o bi nyin: wò o, ikẹhin awọn orilẹ-ède! aginju, ilẹ gbigbẹ, ati ahoro! 13 Nitori ibinu Oluwa li a kì yio gbe inu rẹ̀, ṣugbọn yio dahoro patapata: olukuluku ẹniti o ba re Babeli kọja yio yanu, yio si ṣe ẹlẹya si gbogbo ipọnju rẹ̀. 14 Ẹ tẹgun si Babeli yikakiri: gbogbo ẹnyin ti nfà ọrun, ẹ tafa si i, ẹ máṣe ṣọ́ ọfa lò, nitoriti o ti ṣẹ̀ si Oluwa. 15 Ẹ ho bo o yikakiri: o ti nà ọwọ rẹ̀: ọwọ̀n ìti rẹ̀ ṣubu, a wó odi rẹ̀ lulẹ: nitori igbẹsan Oluwa ni: ẹ gbẹsan lara rẹ̀; gẹgẹ bi o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i. 16 Ke afunrugbin kuro ni Babeli, ati ẹniti ndi doje mu ni igbà ikore! nitori ẹ̀ru idà ti nṣika, olukuluku wọn o yipada si ọdọ enia rẹ̀, olukuluku yio si salọ si ilẹ rẹ̀.

Ìpadàbọ̀ Àwọn Ọmọ Israẹli

17 Israeli jẹ́ agutan ti o ṣina kiri, awọn kiniun ti le e lọ: niṣaju ọba Assiria pa a jẹ, ati nikẹhin yi Nebukadnessari, ọba Babeli, sán egungun rẹ̀. 18 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o jẹ ọba Babeli ati ilẹ rẹ̀ niya, gẹgẹ bi emi ti jẹ ọba Assiria niya. 19 Emi o si tun mu Israeli wá si ibugbe rẹ̀, on o si ma bọ ara rẹ̀ lori Karmeli, ati Baṣani, a o si tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrun li oke Efraimu ati ni Gileadi. 20 Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, li Oluwa wi, a o wá aiṣedẽde Israeli kiri, ṣugbọn kì o si mọ́; ati ẹ̀ṣẹ Juda, a kì o si ri wọn: nitori emi o dariji awọn ti mo mu ṣẹkù.

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Babiloni

21 Goke lọ si ilẹ ọlọtẹ li ọ̀na meji, ani sori rẹ̀ ati si awọn olugbe ilu Ibẹwo: sọ ọ di ahoro ki o si parun lẹhin wọn, li Oluwa wi, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti emi ti paṣẹ fun ọ. 22 Iró ogun ni ilẹ na, ati ti iparun nla! 23 Bawo li a ti fọ, ti a si ṣẹ olú gbogbo ilẹ aiye! Bawo ni Babeli di ahoro lãrin awọn orilẹ-ède! 24 Emi ti kẹ okùn fun ọ, a si mu ọ, iwọ Babeli, iwọ kò si mọ̀: a ri ọ, a si mu ọ pẹlu, nitoripe iwọ ti ba Oluwa ja. 25 Oluwa ti ṣi ile ohun-ijà rẹ̀ silẹ; o si ti mu ohun-elo ikannu rẹ̀ jade: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni iṣẹ́ iṣe ni ilẹ awọn ara Kaldea. 26 Ẹ wá sori rẹ̀ lati opin gbogbo, ṣi ile iṣura rẹ̀ silẹ: ẹ kó o jọ bi òkiti, ki ẹ si yà a sọtọ fun iparun, ẹ máṣe fi iyokù silẹ fun u! 27 Pa gbogbo awọn akọ-malu rẹ̀! nwọn o lọ si ibi pipa: ègbe ni fun wọn! nitori ọjọ wọn de, àkoko ibẹwo wọn. 28 Ohùn awọn ti o salọ, ti o si sala lati ilẹ Babeli wá, lati kede igbẹsan Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni, igbẹsan tempili rẹ̀! 29 Pè ọ̀pọlọpọ enia, ani gbogbo tafatafa, sori Babeli, ẹ dótì i yikakiri; má jẹ ki ẹnikan sala: san fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i, nitoriti o ti gberaga si Oluwa, si Ẹni-Mimọ Israeli. 30 Nitorina ni awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ologun rẹ̀ li a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa wi. 31 Wò o, emi dojukọ ọ! iwọ agberaga, li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, wi: nitori ọjọ rẹ de, àkoko ti emi o bẹ̀ ọ wò. 32 Agberaga yio kọsẹ, yio si ṣubu, ẹnikan kì o si gbe e dide: emi o si da iná ni ilu rẹ̀, yio si jo gbogbo ohun ti o yi i kakiri. 33 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda li a jumọ pọn loju pọ̀: gbogbo awọn ti o kó wọn ni ìgbekun si di wọn mu ṣinṣin; nwọn kọ̀ lati jọ wọn lọwọ lọ. 34 Ṣugbọn Olurapada wọn lagbara; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: ni jijà yio gba ijà wọn jà! ki o le mu ilẹ na simi, ki o si mu awọn olugbe Babeli wariri. 35 Ida lori awọn ara Kaldea, li Oluwa wi, ati lori awọn olugbe Babeli, ati lori awọn ijoye rẹ̀, ati lori awọn ọlọgbọn rẹ̀? 36 Idà lori awọn ahalẹ nwọn o si ṣarán: idà lori awọn alagbara rẹ̀; nwọn o si damu. 37 Idà lori awọn ẹṣin rẹ̀, ati lori awọn kẹ̀kẹ ati lori gbogbo awọn àjeji enia ti o wà lãrin rẹ̀; nwọn o si di obinrin: idà lori iṣura rẹ̀; a o si kó wọn lọ. 38 Ọda lori omi odò rẹ̀; nwọn o si gbẹ: nitori ilẹ ere fifin ni, nwọn si nṣogo ninu oriṣa wọn. 39 Nitorina awọn ẹran-iju pẹlu ọ̀wawa ni yio ma gbe ibẹ̀, abo ògongo yio si ma gbe inu rẹ̀, a kì o si gbe inu rẹ̀ mọ lailai; bẹ̃ni a kì o ṣatipo ninu rẹ̀ lati irandiran. 40 Gẹgẹ bi Ọlọrun ti bì Sodomu ati Gomorra ṣubu ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; bẹ̃ni enia kan kì o gbe ibẹ, tabi ọmọ enia kan kì o ṣatipo ninu rẹ̀. 41 Wò o, orilẹ-ède kan yio wá lati ariwa, ati orilẹ-ède nla, ọba pupọ li o si dide lati opin ilẹ aiye wá. 42 Nwọn o di ọrun ati ọ̀kọ mu: onroro ni nwọn, nwọn kì o si ṣe ãnu: ohùn wọn yio ho gẹgẹ bi okun, nwọn o si gun ori ẹṣin lẹsẹsẹ, nwọn si mura bi ọkunrin ti yio jà ọ logun, iwọ ọmọbinrin Babeli. 43 Ọba Babeli ti gbọ́ iró wọn, ọwọ rẹ̀ si rọ: ẹ̀dun dì i mu, ati irora gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi. 44 Wò o, on o goke wá bi kiniun lati wiwú Jordani si ibugbe okuta; nitori ojiji li emi o le wọn lọ kuro nibẹ; ati tani si li ẹniti a yàn, ti emi o yàn sori rẹ̀? nitori tani dabi emi? tani o si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na ti yio le duro niwaju mi? 45 Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa, ti o ti gba si Babeli: ati èro rẹ̀, ti o ti gba si ilẹ awọn ara Kaldea: lõtọ awọn ti o kere julọ ninu agbo-ẹran: yio wọ́ wọn kiri: lõtọ on o sọ ibugbe di ahoro lori wọn. 46 Nitori ohùn igbe nla pe: a kó Babeli, ilẹ-aiye mì, a si gbọ́ ariwo na lãrin awọn orilẹ-ède.

Jeremiah 51

Ọlọrun Tún Dá Babiloni Lẹ́jọ́ Sí i

1 BAYI li Oluwa wi: wò o, emi o rú afẹfẹ iparun soke si Babeli, ati si awọn ti ngbe ãrin awọn ti o dide si mi; 2 Emi o si rán awọn alatẹ si Babeli, ti yio fẹ ẹ, nwọn o si sọ ilẹ rẹ̀ di ofo: nitori li ọjọ wahala ni nwọn o wà lọdọ rẹ̀ yikakiri. 3 Jẹ ki tafatafa fà ọrun rẹ̀ si ẹniti nfà ọrun, ati si ẹniti o nṣogo ninu ẹ̀wu irin rẹ̀: ẹ má si ṣe dá awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ si, ẹ run gbogbo ogun rẹ̀ patapata. 4 Awọn ti a pa yio si ṣubu ni ilẹ awọn ara Kaldea, awọn ti a gun li ọ̀kọ, yio si ṣubu ni ita rẹ̀. 5 Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli. 6 Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u. 7 Babeli jẹ ago wura lọwọ Oluwa, ti o mu gbogbo ilẹ aiye yo bi ọ̀muti: awọn orilẹ-ède ti mu ninu ọti-waini rẹ̀; nitorina ni awọn orilẹ-ède nṣogo. 8 Babeli ṣubu, a si fọ ọ lojiji: ẹ hu fun u; ẹ mu ikunra fun irora rẹ̀, bi o jẹ bẹ̃ pe, yio san fun u. 9 Awa fẹ wò Babeli sàn, ṣugbọn kò sàn; ẹ kọ̀ ọ silẹ, ki ẹ si jẹ ki a lọ, olukuluku si ilẹ rẹ̀: nitori ẹbi rẹ̀ de ọrun, a si gbe e soke de awọsanma. 10 Oluwa mu ododo wa jade; ẹ wá, ẹ jẹ ki a si kede iṣẹ Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni. 11 Pọ́n ọfa mu: mu asà li ọwọ: Oluwa ti ru ẹmi awọn ọba Media soke: nitori ipinnu rẹ̀ si Babeli ni lati pa a run, nitoripe igbẹsan Oluwa ni, igbẹsan fun tempili rẹ̀. 12 Gbé asia soke lori odi Babeli, mu awọn iṣọ lagbara, mu awọn oluṣọ duro, ẹ yàn ẹ̀bu: nitori Oluwa gbero, o si ṣe eyi ti o wi si awọn olugbe Babeli. 13 Iwọ ẹniti ngbe ẹba omi pupọ, ti o pọ ni iṣura, opin rẹ de, iwọn ikogun-ole rẹ kún. 14 Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ bura pe, ni kikún emi o fi enia kún ọ gẹgẹ bi ẹlẹnga; nwọn o si pa ariwo ogun lori rẹ.

Orin Ìyìn sí Ọlọrun

15 On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti ṣe ipinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si tẹ́ awọn ọrun nipa oye rẹ̀. 16 Nigbati o ba san ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ li oju ọrun; o si mu kũku goke lati opin aiye wá, o dá manamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá. 17 Aṣiwere ni gbogbo enia, nitori oye kò si; oju tì gbogbo alagbẹdẹ nitori ere, nitori ere didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu wọn. 18 Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: ni ìgba ibẹ̀wo wọn, nwọn o ṣegbe. 19 Ipin Jakobu kò dabi wọn: nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo: Israeli si ni ẹ̀ya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

Òòlù OLUWA

20 Iwọ ni òlù mi, ohun elo-ogun: emi o fi ọ fọ awọn orilẹ-ède tũtu, emi o si fi ọ pa awọn ijọba run; 21 Emi o si fi ọ fọ ẹṣin ati ẹlẹṣin tũtu; emi o si fi ọ fọ kẹ̀kẹ ati ẹniti o gùn u tũtu; 22 Emi o si fi ọ fọ ọkunrin ati obinrin tũtu; emi o si fi ọ fọ arugbo ati ọmọde tũtu; emi o si fi ọ fọ ọdọmọkunrin ati wundia tũtu; 23 Emi o si fi ọ fọ oluṣọ-agutan ati agbo-ẹran rẹ̀ tũtu, emi o si fi ọ fọ àgbẹ ati àjaga-malu rẹ̀ tũtu; emi o si fi ọ fọ awọn balẹ ati awọn ijoye tũtu.

Ìjìyà Babiloni

24 Ṣugbọn emi o si san fun Babeli ati fun gbogbo awọn olugbe Kaldea gbogbo ibi wọn, ti nwọn ti ṣe ni Sioni li oju nyin, li Oluwa wi. 25 Wo o, emi dojukọ ọ, iwọ oke ipanirun! li Oluwa wi, ti o pa gbogbo ilẹ aiye run; emi o si nà ọwọ mi sori rẹ, emi o si yi ọ lulẹ lati ori apata wá, emi o si ṣe ọ ni oke jijona. 26 Ki nwọn ki o má le mu okuta igun ile, tabi okuta ipilẹ ninu rẹ, ṣugbọn iwọ o di ahoro lailai, li Oluwa wi. 27 Ẹ gbe asia soke ni ilẹ na, fọn ipè lãrin awọn orilẹ-ède, sọ awọn orilẹ-ède di mimọ́ sori rẹ̀, pè awọn ijọba Ararati, Minni, ati Aṣkinasi sori rẹ̀, yàn balogun sori rẹ̀, mu awọn ẹṣin wá gẹgẹ bi ẹlẹnga ẹlẹgun. 28 Sọ awọn orilẹ-ède pẹlu awọn ọba Media di mimọ́ sori rẹ̀, awọn balẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀. 29 Ilẹ yio si mì, yio si kerora: nitori gbogbo èro Oluwa ni a o mú ṣẹ si Babeli, lati sọ ilẹ Babeli di ahoro laini olugbe. 30 Awọn akọni Babeli ti dẹkun jijà, nwọn ti joko ninu ile-odi wọn; agbara wọn ti tán; nwọn di obinrin, nwọn tinabọ ibugbe rẹ̀; a ṣẹ́ ikere rẹ̀. 31 Ẹnikan ti nsare yio sare lọ lati pade ẹnikeji ti nsare, ati onṣẹ kan lati pade onṣẹ miran, lati jiṣẹ fun ọba Babeli pe: a kó ilu rẹ̀ ni iha gbogbo. 32 Ati pe, a gbà awọn asọda wọnni, nwọn si ti fi ifefe joná, ẹ̀ru si ba awọn ọkunrin ogun. 33 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Ọmọbinrin Babeli dabi ilẹ ipaka, li akoko ti a o pa ọka lori rẹ̀: sibẹ ni igba diẹ si i, akoko ikore rẹ̀ mbọ fun u. 34 Nebukadnessari, ọba Babeli, ti jẹ mi run, o ti tẹ̀ mi mọlẹ, o ti ṣe mi ni ohun-elo ofo, o ti gbe mi mì gẹgẹ bi ọ̀wawa, o ti fi ohun didara mi kún ikun rẹ̀, o ti le mi jade. 35 Ki ìwa-ika ti a hù si mi ati ẹran-ara mi ki o wá sori Babeli, bẹ̃ni iwọ olugbe Sioni yio wi; ati ẹ̀jẹ mi lori awọn olugbe, ara Kaldea, bẹ̃ni iwọ, Jerusalemu, yio wi.

OLUWA Yóo Ran Israẹli lọ́wọ́

36 Nitorina bayi ni Oluwa wi; Wò o, emi o gba ijà rẹ jà, emi o si gba ẹsan rẹ, emi o si gbẹ okun rẹ̀, emi o si mu gbogbo orisun rẹ̀ gbẹ. 37 Babeli yio si di òkiti àlapa, ibugbe ọ̀wawa, iyanu, ẹsin, laini olugbe. 38 Nwọn o jumọ bú bi kiniun: nwọn o si ke bi ọmọ kiniun. 39 Ninu oru wọn li emi o ṣe ase ohun mimu fun wọn, emi o si mu wọn yo bi ọ̀muti, ki nwọn ki o le ma yọ̀, ki nwọn ki o si sun orun lailai, ki nwọn ki o má si jí mọ́, li Oluwa wi. 40 Emi o si mu wọn wá bi ọdọ-agutan si ibi pipa, bi àgbo pẹlu obukọ.

Ìpín Babiloni

41 Bawo li a kó Ṣeṣaki! bawo li ọwọ wọn ṣe tẹ iyìn gbogbo ilẹ aiye! bawo ni Babeli ṣe di iyanu lãrin awọn orilẹ-ède! 42 Okun wá sori Babeli: a si fi ọ̀pọlọpọ riru omi rẹ̀ bò o mọlẹ. 43 Ilu rẹ̀ ni ahoro, ilẹ gbigbe, ati aginju: ilẹ ninu eyiti ẹnikẹni kò gbe, bẹ̃ni ọmọ enia kò kọja nibẹ. 44 Nitori emi o jẹ Beli niya ni Babeli, emi o si mu eyiti o ti gbemì jade li ẹnu rẹ̀: awọn orilẹ-ède kì yio jumọ ṣàn lọ pọ si ọdọ rẹ̀ mọ: lõtọ odi Babeli yio wó. 45 Enia mi, ẹ jade ni ãrin rẹ̀, ki olukuluku nyin si gba ẹmi rẹ̀ là kuro ninu ibinu gbigbona Oluwa! 46 Ati ki ọkàn nyin má ba rẹ̀wẹsi, ati ki ẹ má ba bẹ̀ru, nitori iró ti a o gbọ́ ni ilẹ na; nitori iró na yio de li ọdun na, ati lẹhin na iró yio de li ọdun keji, ati ìwa-ika ni ilẹ na, alakoso yio dide si alakoso. 47 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, ti emi o bẹ awọn ere fifin Babeli wò: oju yio si tì gbogbo ilẹ rẹ̀, gbogbo awọn olupa rẹ̀ yio si ṣubu li ãrin rẹ̀. 48 Ọrun ati aiye, ati gbogbo ohun ti o wà ninu wọn, yio si kọrin lori Babeli: nitori awọn afiniṣeijẹ yio wá sori rẹ̀ lati ariwa, li Oluwa wi. 49 Gẹgẹ bi Babeli ti mu ki awọn olupa Israeli ṣubu, bẹ̃ gẹgẹ li awọn olupa gbogbo ilẹ aiye yio ṣubu.

Ọlọrun Ranṣẹ sí Israẹli ní Babiloni

50 Ẹnyin ti o ti bọ lọwọ idà, ẹ lọ, ẹ má duro: ẹ ranti Oluwa li okere, ẹ si jẹ ki Jerusalemu wá si ọkàn nyin. 51 Oju tì wa, nitoripe awa ti gbọ́ ẹ̀gan: itiju ti bò loju, nitori awọn alejo wá sori ohun mimọ́ ile Oluwa. 52 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o ṣe ibẹwo lori awọn ere fifin rẹ̀: ati awọn ti o gbọgbẹ yio si mã gbin ja gbogbo ilẹ rẹ̀. 53 Bi Babeli tilẹ goke lọ si ọrun, bi o si ṣe olodi li oke agbara rẹ̀, sibẹ awọn afiniṣeijẹ yio ti ọdọ mi tọ̀ ọ wá, li Oluwa wi.

Ìparun Túbọ̀ Dé Bá Babiloni

54 Iró igbe lati Babeli! ati iparun nla lati ilẹ awọn ara Kaldea! 55 Nitoripe Oluwa ti ṣe Babeli ni ijẹ, o si ti pa ohùn nla run kuro ninu rẹ̀; riru wọn si nho bi omi pupọ, a gbọ́ ariwo ohùn wọn. 56 Nitoripe afiniṣeijẹ de sori rẹ̀, ani sori Babeli; a mu awọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nitori Ọlọrun ẹsan ni Oluwa, yio san a nitõtọ. 57 Emi o si mu ki awọn ijoye rẹ̀ yo bi ọ̀muti, ati awọn ọlọgbọn rẹ̀, awọn bàlẹ rẹ̀, ati awọn alakoso rẹ̀, ati awọn akọni rẹ̀, nwọn o si sun orun lailai, nwọn kì o si ji mọ́, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun. 58 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: odi Babeli gbigboro li a o wó lulẹ patapata, ẹnu-bode giga rẹ̀ li a o si fi iná sun: tobẹ̃ ti awọn enia ti ṣiṣẹ lasan, ati awọn orilẹ-ède ti ṣiṣẹ fun iná, ti ãrẹ si mu wọn.

Jeremiah Ranṣẹ sí Babiloni

59 Ọ̀rọ ti Jeremiah woli paṣẹ fun Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maaseiah, nigbati o nlọ niti Sedekiah, ọba Judah, si Babeli li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. Seraiah yi si ni ijoye ibudo. 60 Jeremiah si kọ gbogbo ọ̀rọ-ibi ti yio wá sori Babeli sinu iwe kan, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti a kọ si Babeli. 61 Jeremiah si sọ fun Seraiah pe, nigbati iwọ ba de Babeli, ki iwọ ki o si wò, ki iwọ ki o si ka gbogbo ọ̀rọ wọnyi. 62 Ki iwọ ki o si wipe, Oluwa, iwọ ti sọ̀rọ si ibi yi, lati ke e kuro, ki ẹnikẹni má ṣe gbe inu rẹ̀, ati enia ati ẹran, nitori pe yio di ahoro lailai. 63 Yio si ṣe nigbati iwọ ba pari kikà iwe yi tan, ki iwọ ki o di okuta mọ ọ, ki o si sọ ọ si ãrin odò Ferate: 64 Ki iwọ si wipe, Bayi ni Babeli yio rì, kì o si tun dide kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori rẹ̀: ãrẹ̀ yio si mu wọn. Titi de ihin li ọ̀rọ Jeremiah.

Jeremiah 52

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 SEDEKIAH jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹrẹ si ijọba, o si jọba, ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah, ara Libna. 2 On si ṣe buburu niwaju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe. 3 Nitori ibinu Oluwa, o ri bẹ̃ ni Jerusalemu ati Juda, titi o fi tì wọn jade kuro niwaju rẹ̀. Sedekiah si ṣọtẹ si ọba Babeli. 4 O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, Nebukadnessari, ọba Babeli de, on ati gbogbo ogun rẹ̀ si Jerusalemu, o si dó tì i, o si mọdi tì i yikakiri. 5 A si há ilu na mọ titi di ọdun ikọkanla Sedekiah ọba. 6 Ati li oṣu kẹrin li ọjọ kẹsan oṣu, ìyan mu gidigidi ni ilu, tobẹ̃ ti kò si onjẹ fun awọn enia ilẹ na. 7 Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ. 8 Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa ọba, nwọn si ba Sedekiah ni pẹtẹlẹ Jeriko, gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀. 9 Nwọn si mu ọba, nwọn si mu u goke wá si ọdọ ọba Babeli ni Ribla, ni ilẹ Hamati; o si sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀. 10 Ọba Babeli si pa awọn ọmọ Sedekiah niwaju rẹ̀: o pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu ni Ribla. 11 Pẹlupẹlu ọba Babeli fọ Sedekiah li oju; o si fi ẹ̀wọn dè e, o si mu u lọ si Babeli, o si fi sinu tubu titi di ọjọ ikú rẹ̀.

Wọ́n Wó Tẹmpili Lulẹ̀

12 Njẹ li oṣu karun, li ọjọ kẹwa oṣu, ti o jẹ ọdun kọkandilogun Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ti o nsin ọba Babeli, wá si Jerusalemu. 13 O si kun ile Oluwa, ati ile ọba; ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile nla li o fi iná sun. 14 Ati gbogbo ogun awọn ara Kaldea, ti nwọn wà pẹlu balogun iṣọ, wó gbogbo odi Jerusalemu lulẹ yikakiri. 15 Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó ninu awọn talaka awọn enia, ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu, ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ya lọ, ti o si ya tọ̀ ọba Babeli lọ, ati iyokù awọn ọ̀pọ enia na. 16 Nebusaradani, balogun iṣọ, si fi ninu awọn talaka ilẹ na silẹ lati mã ṣe alabojuto ajara ati lati ma ṣe alaroko. 17 Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ lẹba ile Oluwa, ati ijoko wọnni ati agbada idẹ nla ti o wà ni ile Oluwa ni awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó gbogbo idẹ wọn lọ si Babeli. 18 Ati ìkoko wọnni, ati ọkọ́ wọnni, ati alumagaji fitila wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun elo idẹ wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ isin, ni nwọn kó lọ. 19 Ati awo-koto wọnni, ati ohun ifọnna wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ìkoko wọnni, ati ọpa fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati ago wọnni, eyiti iṣe ti wura, wura, ati eyiti iṣe ti fadaka, fadaka, ni balogun iṣọ kó lọ. 20 Awọn ọwọ̀n meji, agbada nla kan, ati awọn malu idẹ mejila ti o wà labẹ ijoko, ti Solomoni ọba, ti ṣe fun ile Oluwa: idẹ gbogbo ohun-elo wọnyi alaini iwọ̀n ni. 21 Ati ọwọ̀n mejeji, giga ọwọ̀n kan ni igbọnwọ mejidilogun; okùn igbọnwọ mejila si yi i ka; ninipọn wọn si jẹ ika mẹrin, nwọn ni iho ninu. 22 Ati ọna-ori idẹ wà lori rẹ̀; giga ọna-ori kan si ni igbọnwọ marun, pẹlu iṣẹ wiwun ati pomegranate lara ọna ori wọnni yikakiri, gbogbo rẹ̀ jẹ ti idẹ: gẹgẹ bi wọnyi ni ọwọ̀n ekeji pẹlu, ati pomegranate rẹ̀. 23 Pomegranate mẹrindilọgọrun li o wà ni gbangba: gbogbo pomegranate lori iṣẹ wiwun na jẹ ọgọrun yikakiri.

Wọ́n Kó Àwọn Ará Juda ní Ìgbèkùn Lọ sí Babiloni

24 Balogun iṣọ si mu Seraiah, olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah, alufa keji, ati awọn oluṣọ iloro mẹta: 25 Ati lati inu ilu o mu iwẹfa kan, ti o ni itọju awọn ologun; ati awọn ọkunrin meje ti nwọn nduro niwaju ọba, ti a ri ni ilu na; ati akọwe olori ogun ẹniti ntò awọn enia ilẹ na; ati ọgọta enia ninu awọn enia ilẹ na, ti a ri li ãrin ilu na. 26 Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu wọn, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla. 27 Ọba Babeli si kọlu wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀. 28 Eyi li awọn enia ti Nebukadnessari kó ni ìgbekun lọ: li ọdun keje, ẹgbẹdogun o le mẹtalelogun ara Juda. 29 Li ọdun kejidilogun Nebukadnessari, o kó ẹgbẹrin enia o le mejilelọgbọn ni igbèkun lati Jerusalemu lọ: 30 Li ọdun kẹtalelogun Nebukadnessari, Nebusaradani, balogun iṣọ, kó ọtadilẹgbẹrin enia o di marun awọn ara Juda ni igbekun lọ: gbogbo awọn enia na jẹ ẹgbẹtalelogun. 31 O si ṣe, li ọdun kẹtadilogoji Jehoiakimu, ọba Juda, li oṣu kejila, li ọjọ kẹdọgbọn oṣu, Efil-Merodaki, ọba Babeli, li ọdun ekini ijọba rẹ̀, o gbe ori Jehoiakimu, ọba Juda, soke, o si mu u jade ninu ile túbu. 32 O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbe itẹ rẹ̀ ga jù itẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli. 33 O si parọ aṣọ túbu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀. 34 Ati ipin onjẹ rẹ̀, ipin onjẹ igbagbogbo, ti ọba Babeli nfi fun u lojojumọ ni ipin tirẹ̀, titi di ọjọ ikú rẹ̀, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

Ẹkún 1

Ìbànújẹ́ Jerusalẹmu

1 BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú! 2 On sọkun gidigidi li oru, omije rẹ̀ si wà ni ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: lãrin gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikẹni lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ ti ba a lo ẹ̀tan, nwọn di ọta rẹ̀. 3 Juda lọ si àjo nitori ipọnju ati isin-ẹrú nla: o joko lãrin awọn orilẹ-ède, on kò ri isimi: gbogbo awọn ti nlepa rẹ̀ ba a ni ibi hiha. 4 Ọ̀na Sioni wọnni nṣọ̀fọ, nitori ẹnikan kò wá si ajọ-mimọ́: gbogbo ẹnu-bode rẹ̀ dahoro: awọn alufa rẹ̀ kẹdun, awọn wundia rẹ̀ nkãnu, on si wà ni kikoro ọkàn. 5 Awọn aninilara rẹ̀ bori, awọn ọta rẹ̀ ri rere: nitori Oluwa ti pọn ọ loju nitori ọ̀pọlọpọ irekọja rẹ̀; awọn ọmọ wẹrẹ rẹ̀ lọ si igbekun niwaju awọn aninilara. 6 Gbogbo ẹwà ọmọbinrin Sioni si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀: awọn ijoye rẹ̀ dabi agbọnrin ti kò ri pápá oko tutu, nwọn si lọ laini agbara niwaju alepa nì, 7 Li ọjọ ipọnju rẹ̀ ati inilara rẹ̀ ni Jerusalemu ranti gbogbo ohun daradara ti o ti ni li ọjọ igbãni, nigbati awọn enia rẹ̀ ṣubu si ọwọ ọta, ẹnikan kò si ràn a lọwọ: awọn aninilara ri i, nwọn si fi iparun rẹ̀ ṣẹsin. 8 Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada. 9 Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori! 10 Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ. 11 Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn wá onjẹ; nwọn fi ohun daradara fun onjẹ lati tu ara wọn ninu. Wò o, Oluwa, ki o si rò! nitori emi di ẹni-ẹ̀gan. 12 Kò ha kàn nyin bi, gbogbo ẹnyin ti nkọja? Wò o, ki ẹ si ri bi ibanujẹ kan ba wà bi ibanujẹ mi, ti a ṣe si mi! eyiti Oluwa fi pọn mi loju li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀. 13 Lati oke li a ti rán iná sinu egungun mi, o si ràn ninu rẹ̀: On ti nà àwọn fun ẹsẹ mi, o ti yi mi pada sẹhin; O ti mu mi dahoro, mo si rẹ̀wẹsi lojojumọ. 14 Okùn àjaga irekọja mi li a dimu li ọwọ rẹ̀; a so wọn pọ̀: nwọn yi ọrùn mi ka, nwọn tẹ agbara mi mọlẹ; Oluwa ti fi mi le ọwọ awọn ẹniti emi kò le dide si. 15 Oluwa ti tẹ̀ gbogbo awọn akọni mi mọlẹ labẹ ẹsẹ li arin mi: On ti pe apejọ sori mi lati tẹ̀ awọn ọdọmọkunrin mi rẹ́: Oluwa ti tẹ ifunti fun wundia, ọmọbinrin Juda. 16 Emi nsọkun nitori nkan wọnyi; oju mi! oju mi ṣàn omi silẹ, nitoripe olutunu ati ẹniti iba mu ọkàn mi sọji jina si mi: awọn ọmọ mi run, nitoripe ọta bori. 17 Sioni nà ọwọ rẹ̀ jade, kò si sí ẹnikan lati tù u ninu: Oluwa ti paṣẹ niti Jakobu pe, ki awọn aninilara rẹ̀ ki o yi i kakiri: Jerusalemu dabi obinrin ẹlẹgbin lãrin wọn. 18 Oluwa ṣe olododo; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ ẹnu rẹ̀: gbọ́, (emi bẹ nyin,) gbogbo orilẹ-ède, ẹ si wò ikãnu mi; awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi lọ si igbekun. 19 Emi pè awọn olufẹ mi, awọn wọnyi tàn mi jẹ: awọn alufa mi, ati àgbagba mi jọwọ ẹmi wọn lọwọ ni ilu, nigbati nwọn nwá onjẹ wọn lati mu ẹmi wọn sọji. 20 Wò o, Oluwa: nitoriti emi wà ninu ipọnju: inu mi nhó; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode, idà sọni di alailọmọ, ni ile, o dabi ikú! 21 Nwọn gbọ́ bi emi ti nkẹdùn to: sibẹ kò si olutunu fun mi: gbogbo awọn ọta mi gbọ́ iyọnu mi; inu wọn dùn nitori iwọ ti ṣe e: iwọ o mu ọjọ na wá ti iwọ ti dá, nwọn o si ri gẹgẹ bi emi. 22 Jẹ ki gbogbo ìwa-buburu wọn wá si iwaju rẹ; si ṣe si wọn, gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si mi nitori gbogbo irekọja mi: nitori ikẹdùn mi pọ̀, ọkàn mi si rẹ̀wẹsi.

Ẹkún 2

Ìyà Tí OLUWA Fi Jẹ Jerusalẹmu

1 BAWO li Oluwa ti fi awọsanma bo ọmọbinrin Sioni ni ibinu rẹ̀! ti o sọ ẹwa Israeli kalẹ lati oke ọrun wá si ilẹ, ti kò si ranti apoti-itisẹ rẹ̀ li ọjọ ibinu rẹ̀! 2 Oluwa ti gbe gbogbo ibugbe Jakobu mì, kò si da a si: o ti wó ilu-odi ọmọbinrin Juda lulẹ, ninu irunu rẹ̀ o ti lù wọn bolẹ: o ti sọ ijọba na ati awọn ijoye rẹ̀ di alaimọ́. 3 O ti ke gbogbo iwo Israeli kuro ninu ibinu gbigbona rẹ̀: o ti fà ọwọ ọtun rẹ̀ sẹhin niwaju ọta, o si jo gẹgẹ bi ọwọ iná ninu Jakobu ti o jẹrun yikakiri. 4 O ti fà ọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọta: o duro, o mura ọwọ ọtun rẹ̀ gẹgẹ bi aninilara, o si pa gbogbo ohun didara ti oju fẹ iri ni agọ ọmọbinrin Sioni, o dà irunu rẹ̀ jade bi iná. 5 Oluwa jẹ gẹgẹ bi ọta: o ti gbe Israeli mì, o ti gbe gbogbo ãfin rẹ̀ mì: o ti pa ilu olodi rẹ̀ run o si ti fi ibanujẹ lori ibanujẹ fun ọmọbinrin Juda. 6 O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀. 7 Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́. 8 Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ. 9 Ẹnu-bode rẹ̀ wọnni rì si ilẹ; o ti parun o si ṣẹ́ ọpá idabu rẹ̀; ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn orilẹ-ède: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa. 10 Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ. 11 Oju mi gbẹ tan fun omije, inu mi nho, a dà ẹ̀dọ mi sori ilẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi: nitoripe awọn ọmọ wẹ̃rẹ ati awọn ọmọ-ọmu nkulọ ni ita ilu na. 12 Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn. 13 Kili ohun ti emi o mu fi jẹri niwaju rẹ? kili ohun ti emi o fi ọ we, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o fi ba ọ dọgba, ki emi ba le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitoripe ọgbẹ rẹ tobi gẹgẹ bi okun; tali o le wò ọ sàn? 14 Awọn woli rẹ ti riran ohun asan ati wère fun ọ: nwọn kò si ti fi aiṣedede rẹ hàn ọ, lati yi igbekun rẹ pada kuro; ṣugbọn nwọn ti riran ọ̀rọ-wiwo eke fun ọ ati imuniṣina. 15 Gbogbo awọn ti nkọja patẹwọ le ọ; nwọn nṣẹsin, nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu; pe, Ilu na ha li eyi, ti a npè ni: Pipe-ẹwà, Ayọ̀ gbogbo ilẹ aiye! 16 Gbogbo awọn ọta rẹ ya ẹnu wọn si ọ; nwọn nṣe ṣiọ! nwọn si npa ehin keke, nwọn wipe: Awa ti gbe e mì; dajudaju eyi li ọjọ na ti awa ti nwọ̀na fun; ọwọ ti tẹ̀ ẹ, awa ti ri i! 17 Oluwa ti ṣe eyi ti o ti rò; o ti mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti paṣẹ li ọjọ igbãni: o ti bì ṣubu, kò si dasi: o si ti mu ọta yọ̀ lori rẹ, o ti gbe iwo awọn aninilara rẹ soke. 18 Ọkàn wọn kigbe si Oluwa, iwọ odi ọmọbinrin Sioni, jẹ ki omije ṣan silẹ gẹgẹ bi odò lọsan ati loru; má fun ara rẹ ni isimi; máṣe jẹ ki ẹyin oju rẹ gbe jẹ. 19 Dide, kigbe soke li oru ni ibẹrẹ akoko iṣọ: tú ọkàn rẹ jade gẹgẹ bi omi niwaju Oluwa: gbe ọwọ rẹ soke si i fun ẹmi awọn ọmọ wẹwẹ rẹ, ti nkulọ fun ebi ni gbogbo ori-ita. 20 Wò o, Oluwa, ki o rò, fun tani iwọ ti ṣe eyi? Awọn obinrin ha le ma jẹ eso-inu wọn, awọn ọmọ-ọwọ ti nwọn npọ̀n? a ha le ma pa alufa ati woli ni ibi mimọ́ Oluwa? 21 Ewe ati arugbo dubulẹ ni ita wọnni: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ṣubu nipa idà: iwọ ti pa li ọjọ ibinu rẹ; iwọ ti pa, iwọ kò si dasi. 22 Iwọ ti kepe ẹ̀ru mi yikakiri gẹgẹ bi li ọjọ mimọ́, tobẹ̃ ti ẹnikan kò sala tabi kì o kù li ọjọ ibinu Oluwa: awọn ti mo ti pọ̀n ti mo si tọ́, ni ọta mi ti run.

Ẹkún 3

Ìjìyà, Ìrònúpìwàdà ati Ìrètí

1 EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. 2 O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. 3 Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. 4 O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. 5 O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. 6 O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. 7 O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo 8 Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ. 9 O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po. 10 On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ. 11 O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro. 12 O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀. 13 O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ. 14 Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ. 15 O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala. 16 O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru. 17 Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere. 18 Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa. 19 Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. 20 Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. 21 Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. 22 Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. 23 Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. 24 Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. 25 Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. 26 O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa. 27 O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀. 28 Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀. 29 Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà: 30 Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata. 31 Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai: 32 Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. 33 Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ. 34 Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. 35 Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ. 36 Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i? 37 Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀. 38 Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá? 39 Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀! 40 Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa. 41 Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun. 42 Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji. 43 Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi. 44 Iwọ ti fi awọsanma bo ara rẹ, ki adura má le là kọja. 45 Iwọ ti ṣe wa bi idarọ ati ohun alainilãri li ãrin awọn orilẹ-ède. 46 Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa. 47 Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun. 48 Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi. 49 Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi. 50 Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá, 51 Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi. 52 Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi. 53 Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi. 54 Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe! 55 Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá. 56 Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi. 57 Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru! 58 Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada. 59 Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi! 60 Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi. 61 Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi. 62 Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ. 63 Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn. 64 San ẹsan fun wọn, Oluwa, gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn! 65 Fun wọn ni ifọju ọkàn, ègun rẹ lori wọn! 66 Fi ibinu lepa wọn, ki o si pa wọn run kuro labẹ ọrun Oluwa!

Ẹkún 4

Jerusalẹmu, Lẹ́yìn Ìṣubú Rẹ̀

1 BAWO ni wura ṣe di baibai! bawo ni wura didara julọ ṣe pada! okuta ibi-mimọ́ li a tuka ni gbogbo ori ita. 2 Awọn ọmọ iyebiye Sioni, ti o niye lori bi wura didara, bawo li a ṣe kà wọn si bi ikoko amọ̀, iṣẹ ọwọ alamọ̀! 3 Ani ọ̀wawa nfà ọmu jade, nwọn nfi ọmu fun awọn ọmọ wọn: ṣugbọn ọmọbinrin awọn enia mi ti di ìka, gẹgẹ bi abo ògongo li aginju. 4 Ahọn ọmọ-ọmu lẹ̀ mọ oke ẹnu rẹ̀ nitori ongbẹ: awọn ọmọ kekere mbere onjẹ, ẹnikan kò si bu u fun wọn. 5 Awọn ti o ti njẹ ohun didùndidùn nkú lọ ni ita: awọn ti a ti tọ́ ninu aṣọ-òdodó, gbá ãtàn mọra. 6 Nitori aiṣedede ọmọbinrin awọn enia mi tobi jù ẹ̀ṣẹ Sodomu lọ, ti a bì ṣubu ni iṣẹju, laisi iṣiṣẹ ọwọ ninu rẹ̀. 7 Awọn Nasire rẹ̀ mọ́ jù ẹ̀gbọn-owu, nwọn funfun jù wàra; irisi wọn pọn jù iyùn, apẹrẹ wọn dabi okuta Safire: 8 Oju wọn dudu jù ẽdu nisisiyi; a kò mọ̀ wọn ni ita: àwọ wọn lẹ mọ egungun wọn; o di gbigbẹ gẹgẹ bi igi. 9 Awọn ti a fi idà pa san jù awọn ti a fi ebi pa, ti ndaku, ti a gún wọn lara nitori aisi eso-oko. 10 Ọwọ awọn obinrin alãnu ti sè awọn ọmọ awọn tikarawọn: awọn wọnyi li ohun jijẹ fun wọn ni igba wahala ọmọbinrin awọn enia mi. 11 Oluwa ti ṣe aṣepe irunu rẹ̀; o ti dà ibinu gbigbona rẹ̀ jade, o ti dá iná ni Sioni, ti o si ti jo ipilẹ rẹ̀ run. 12 Awọn ọba aiye, ati gbogbo olugbe ilẹ-aiye, kò gbagbọ pe aninilara ati ọta iba ti wọ inu ẹnu-bode Jerusalemu. 13 Nitori ẹ̀ṣẹ awọn woli rẹ̀, ati aiṣedede awọn alufa rẹ̀, ti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn olododo silẹ li ãrin rẹ̀. 14 Nwọn ti rin kiri bi afọju ni ita, nwọn di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ tobẹ̃ ti enia kò le fi ọwọ kan aṣọ wọn. 15 Nwọn nkigbe si wọn pe, ẹ lọ! alaimọ́ ni! ẹ lọ! ẹ lọ! ẹ máṣe fi ọwọ kan a! nigbati nwọn salọ, nwọn si rìn kiri pẹlu: nwọn nwi lãrin awọn orilẹ-ède pe, awọn kì o ṣatipo nibẹ mọ. 16 Oju Oluwa ti tú wọn ka: on kì o fiyesi wọn mọ: nwọn kò buyin fun awọn alufa, nwọn kò ṣãnu fun awọn àgbagba. 17 Bi o ṣe ti wa ni, oju wa nwọ̀na siwaju ati siwaju, fun iranlọwọ wa ti o jẹ asan: lori ile-iṣọ wa, awa nwọ̀na fun orilẹ-ède, ti kò le ràn ni lọwọ. 18 Nwọn dẹkun si ipa ọ̀na wa, ti awa kò le rìn ita wa: opin wa sunmọ tosi, ọjọ wa pé; nitori opin wa de. 19 Awọn ti nlepa wa yara jù idì ọrun lọ: nwọn nlepa wa lori oke wọnni, nwọn bà dè wa li aginju. 20 Ẽmi iho imu wa, ani ẹni-ororo Oluwa, ni a mu ninu ọ̀fin wọn, niti ẹniti awa wipe, labẹ ojiji rẹ̀ li awa o ma gbé lãrin awọn orilẹ-ède. 21 Yọ̀, ki inu rẹ si dùn, iwọ ọmọbinrin Edomu, ti ngbe inu ilẹ Usi; sibẹ ago na yio kọja sọdọ rẹ pẹlu: iwọ o si yo bi ọ̀muti, a o si tu ọ ni ihoho. 22 A mu aiṣedede rẹ kuro, iwọ ọmọbinrin Sioni: on kì o si tun mu ọ lọ si igbekun mọ: On o bẹ̀ aiṣedede rẹ wò, iwọ ọmọbinrin Edomu; yio si fi ẹ̀ṣẹ rẹ hàn.

Ẹkún 5

Adura fún Àánú

1 RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa! 2 A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji. 3 Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó. 4 Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa. 5 Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi. 6 Awa ti fi ọwọ wa fun awọn ara Egipti, ati fun ara Assiria, lati fi onjẹ tẹ́ wa lọrùn. 7 Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn. 8 Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn. 9 Ninu ewu ẹmi wa li awa nlọ mu onjẹ wa, nitori idà ti aginju. 10 Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na. 11 Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda. 12 A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba. 13 Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi. 14 Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn. 15 Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ. 16 Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀. 17 Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai. 18 Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀. 19 Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran! 20 Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ? 21 Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni. 22 Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi?

Esekieli 1

ÌRAN TÍ ỌLỌRUN KỌ́KỌ́ FI HAN ESEKIẸLI

Ìtẹ́ Ọlọrun

1 O si ṣe ọgbọ̀n ọdun, ni oṣu ẹkẹrin, li ọjọ ẹkarun oṣu, bi mo ti wà lãrin awọn igbekùn leti odo Kebari, ọrun ṣi, mo si ri iran Ọlọrun. 2 Li ọjọ karun oṣu, ti iṣe ọdun karun igbekùn Jehoiakini ọba, 3 Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Esekieli alufa, ọmọ Busi wá papã, ni ilẹ awọn ara Kaldea leti odò Kebari, ọwọ́ Oluwa si wà li ara rẹ̀ nibẹ. 4 Mo si wò, si kiye si i, ãja jade wá lati ariwa, awọsanma nla, ati iná ti o yi ara rẹ̀ ka, didán si wà yika, ani lati ãrin rẹ̀ wá, bi àwọ amberi, lati ãrin iná na wá. 5 Pẹlupẹlu lati ãrin rẹ̀ wá, aworan ẹda alãye mẹrin, eyi si ni irí wọn, nwọn ni aworan enia. 6 Olukuluku si ni oju mẹrin, olukuluku si ni iyẹ mẹrin. 7 Ẹsẹ wọn si tọ́, atẹlẹsẹ wọn si dabi atẹlẹsẹ ọmọ malũ: nwọn si tàn bi awọ̀ idẹ didan. 8 Nwọn si ni ọwọ́ enia labẹ iyẹ́ wọn, li ẹgbẹ wọn mẹrẹrin, awọn mẹrẹrin si ni oju wọn ati iyẹ́ wọn. 9 Iyẹ́ wọn si kàn ara wọn; nwọn kò yipada nigbati nwọn lọ, olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran. 10 Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì. 11 Bayi li oju wọn ri: iyẹ́ wọn si nà soke, iyẹ́ meji olukuluku wọn kàn ara wọn, meji si bo ara wọn. 12 Olukuluku wọn si lọ li ọkankan ganran: nibiti ẹmi ibá lọ, nwọn lọ; nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ. 13 Niti aworan awọn ẹda alãye na, irí wọn dabi ẹṣẹ́ iná, ati bi irí inà fitila: o lọ soke ati sodo, lãrin awọn ẹda alãye na, iná na si mọlẹ, manamana si jade lati inu iná na wá. 14 Awọn ẹda alãye na si sure, awọn si pada bi kíkọ manamana. 15 Bi mo si ti wo awọn ẹda alãye na, kiyesi i, kẹkẹ́ kan wà lori ilẹ aiye lẹba awọn ẹda alãye na, pẹlu oju rẹ̀ mẹrin. 16 Irí awọn kẹkẹ́ na ati iṣẹ wọn dabi awọ̀ berili: awọn mẹrẹrin ni aworan kanna; irí wọn ati iṣẹ wọn dabi ẹnipe kẹkẹ́ li ãrin kẹkẹ́. 17 Nigbati nwọn lọ, nwọn fi iha wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ. 18 Niti oruka wọn, nwọn ga tobẹ̃ ti nwọn fi ba ni li ẹ̀ru; oruka wọn si kún fun oju yi awọn mẹrẹrin ka. 19 Nigbati awọn ẹda alãye na lọ, awọn kẹkẹ́ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati a si gbe awọn ẹda alãye na soke, kuro lori ilẹ, a gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu. 20 Nibikibi ti ẹmi ni iba lọ, nwọn lọ; nibẹ li ẹmi fẹ ilọ: a si gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu wọn; nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na. 21 Nigbati wọnni lọ, wọnyi lọ; nigbati a gbe wọnni duro, wọnyi duro; ati nigbati a gbe wọnni soke kuro lori ilẹ a gbe kẹkẹ́ soke pẹlu wọn: nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na. 22 Aworan ofurufu li ori ẹda alãye na dabi àwọ kristali ti o ba ni li ẹ̀ru, ti o nà sori wọn loke. 23 Iyẹ́ wọn si tọ́ labẹ ofurufu, ekini si ekeji: olukuluku ni meji, ti o bo ihà ihín, olukuluku si ni meji ti o bo iha ọhún ara wọn. 24 Nigbati nwọn si lọ, mo gbọ́ ariwo iyẹ́ wọn, bi ariwo omi pupọ, bi ohùn Olodumare, ohùn ọ̀rọ bi ariwo ogun: nigbati nwọn duro, nwọn rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ. 25 Ohùn kan ti inu ofurufu ti o wà lori wọn wá, nigbati nwọn duro, ti nwọn si ti rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ. 26 Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà. 27 Mo si ri bi awọ amberi, bi irí iná yika ninu rẹ̀, lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de oke, ati lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de isalẹ, mo ri bi ẹnipe irí iná, o si ni didan yika. 28 Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.

Esekieli 2

1 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, duro li ẹsẹ rẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ. 2 Ẹmi si wọ inu mi, nigbati o ba mi sọ̀rọ o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, mo si gbọ́ ẹniti o ba mi sọrọ. 3 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, emi ran ọ si awọn ọmọ Israeli, si ọlọtẹ̀ orilẹ-ède, ti o ti ṣọtẹ si mi: awọn ati baba wọn ti ṣẹ̀ si mi titi di oni oloni. 4 Nitori ọmọ alafojudi ati ọlọkàn lile ni nwọn, Emi rán ọ si wọn; iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi. 5 Ati awọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀, (nitori ọlọtẹ̀ ile ni nwọn) sibẹ nwọn o mọ̀ pe woli kan ti wà larin wọn. 6 Ati iwọ, ọmọ enia, máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bi ẹgun ọgàn ati oṣuṣu tilẹ pẹlu rẹ, ti iwọ si gbe ãrin akẽkẽ: máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bẹ̃ni ki o máṣe foya wiwò wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọtẹ̀ ile. 7 Iwọ o si sọ ọ̀rọ mi fun wọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi wọn o kọ̀: nitoriti nwọn jẹ ọlọtẹ̀. 8 Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, gbọ́ ohun ti mo sọ fun ọ; Iwọ máṣe jẹ ọlọtẹ̀ bi ọlọtẹ̀ ile nì: ya ẹ̀nu rẹ, ki o si jẹ ohun ti mo fi fun ọ. 9 Nigbati mo wò, si kiye si i, a ran ọwọ́ kan si mi; si kiye si i, iká-iwé kan wà ninu rẹ̀. 10 O si tẹ́ ẹ siwaju mi, a si kọ ọ ninu ati lode: a si kọ ohùn-reré-ẹkun, ati ọ̀fọ, ati egbé.

Esekieli 3

1 PẸLUPẸLU o wi fun mi pe, Ọmọ enia, jẹ ohun ti iwọ ri, jẹ iká-iwé yi, si lọ ba ile Israeli sọrọ. 2 Mo si ya ẹnu mi, o si mu mi jẹ iká-iwé na. 3 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, mu ki ikùn rẹ jẹ, ki o si fi iká-iwé yi ti emi fi fun ọ kún inu rẹ. Nigbana ni mo jẹ ẹ, o si dabi oyin li ẹnu ni didùn. 4 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Lọ, tọ̀ ile Israeli lọ ki o si fi ọ̀rọ mi ba wọn sọrọ. 5 Nitori a kò ran ọ si enia ède ajeji ati sisọrọ, ṣugbọn si ile Israeli. 6 Ki iṣe si ọ̀pọlọpọ enia ède ajeji, ati ède sisọrọ, ọ̀rọ ẹniti iwọ kò le gbọ́. Nitotọ emi iba rán ọ si wọn, nwọn iba gbọ́ tirẹ. 7 Ṣugbọn ile Israeli kò ni gbọ́ tirẹ; nitori ti nwọn kò fẹ gbọ́ ti emi: nitori alafojudi ati ọlọkàn lile ni gbogbo ile Israeli. 8 Kiyesi i, mo ti sọ oju rẹ di lile si oju wọn, ati iwaju rẹ di lile si iwaju wọn. 9 Bi okuta diamondi ti o le ju okuta ibọn ni mo ṣe iwaju rẹ: máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe fòya oju wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile. 10 Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gba gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ si ọkàn rẹ, si fi eti rẹ gbọ́ wọn. 11 Si lọ, tọ̀ awọn ti igbekùn lọ, awọn ọmọ enia rẹ, si ba wọn sọ̀rọ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀. 12 Ẹmi si gbe mi soke, mo si gbọ́ ohùn iró nla lẹhin mi, nwipe, Ibukun ni fun ogo Oluwa lati ipò rẹ̀ wá. 13 Mo si gbọ́ ariwo iyẹ́ awọn ẹ̀da alãye, ti o kàn ara wọn, ati ariwo awọn kẹkẹ́ ti o wà pẹlu wọn, ati ariwo iró nla. 14 Bẹ̃ni ẹmi na gbe mi soke, o si mu mi kuro, mo si lọ ni ibinujẹ, ati ninu gbigbona ọkàn mi; ṣugbọn ọwọ́ Oluwa le lara mi. 15 Nigbana ni mo tọ̀ awọn ti igbekùn ti Telabibi lọ, ti nwọn ngbe ẹba odò Kebari, mo si joko nibiti nwọn joko, ẹnu si yà mi bi mo ti wà lãrin wọn ni ijọ meje. 16 O si di igbati o ṣe li opin ijọ meje, ọ̀rọ Oluwa wá sọdọ mi, wipe: 17 Ọmọ enia, mo ti fi iwọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli, nitorina gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, si kilọ fun wọn lati ọdọ mi wá. 18 Nigbati emi wi fun enia buburu pe, Iwọ o kú nitõtọ; ti iwọ kò si kilọ̀ fun u, ti iwọ kò sọ̀rọ lati kilọ fun enia buburu, lati kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, lati gba ẹmi rẹ̀ là; enia buburu na yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ. 19 Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ̀ fun enia buburu, ti kò si kuro ninu buburu rẹ̀, ti ko yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ọrun rẹ mọ́. 20 Ẹ̀wẹ, nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si da ẹ̀ṣẹ, ti mo si fi ohun idigbolu siwaju rẹ, yio kú; nitoriti iwọ kò kilọ fun u, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a ki yio ranti ododo rẹ̀ ti o ti ṣe; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ. 21 Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ fun olododo, ki olododo ki o má dẹ̀ṣẹ, ti on kò si ṣẹ̀, yio yè nitotọ, nitori ti a kilọ fun u, ọrùn rẹ si mọ́. 22 Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi nibẹ; o si wi fun mi pe, Dide, lọ si pẹtẹlẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ nibẹ. 23 Mo si dide, mo si lọ si pẹtẹlẹ, si kiyesi i ogo Oluwa duro nibẹ, bi ogo ti mo ri lẹba odò Kebari: mo si doju mi bolẹ. 24 Ẹmi si wọ̀ inu mi lọ, o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, o si ba mi sọ̀rọ, o si sọ fun mi pe, Lọ, há ara rẹ mọ ile rẹ. 25 Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, kiyesi i, nwọn o si fi idè le ọ, nwọn o si fi dè ọ, iwọ ki yio si jade larin wọn. 26 Emi o si mu ahọn rẹ lẹ mọ oke ẹnu rẹ, iwọ o si yadi, iwọ ki yio jẹ abaniwi si wọn; nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn. 27 Ṣugbọn nigbati mo ba bá ọ sọ̀rọ, emi o ya ẹnu rẹ, iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹniti o gbọ́, jẹ ki o gbọ́; ẹniti o kọ̀, jẹ ki o kọ̀ nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.

Esekieli 4

Esekiẹli Gbé Òfin Jáde lórí Ìwà Ìbàjẹ́ ní Jerusalẹmu

1 IWỌ, ọmọ enia, mu awo kan, ki o si fi si iwaju rẹ, ki o si ṣe aworan ilu Jerusalemu sinu rẹ̀. 2 Ki o si dótì i, ki o si mọ ile iṣọ tì i, ki o si mọ odi tì i, ki o si gbe ogun si i, ki o si to õlù yi i ka. 3 Mu awo irin kan, ki o si gbe e duro bi odi irin lãrin rẹ ati ilu na: ki o si kọju si i, a o si dótì i, iwọ o si dótì i. Eyi o jẹ àmi si ile Israeli. 4 Fi iha osì rẹ dubulẹ, ki o si fi ẹ̀ṣẹ ile Israeli sori rẹ̀: gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ sori rẹ̀ ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ wọn. 5 Nitori mo ti fi ọdun ẹ̀ṣẹ wọn le ọ lori, gẹgẹ bi iye ọjọ na, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ: bẹ̃ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ ile Israeli. 6 Nigbati iwọ ba si pari wọn, tun fi ẹgbẹ́ rẹ ọtún dubulẹ, iwọ o si ru ẹ̀ṣẹ ile Juda li ogoji ọjọ: mo ti yàn ọjọ kan fun ọdun kan fun ọ. 7 Nitorina iwọ o kọju si didótì Jerusalemu, iwọ ki yio si bo apá rẹ, iwọ o si sọ asọtẹlẹ si i. 8 Si kiyesi i, emi o fi idè le ara rẹ, iwọ ki yio si yipada lati ihà kan de ekeji, titi iwọ o fi pari gbogbo ọjọ didotì rẹ. 9 Si mu alikama, ati ọka bàba, erẽ ati lentile ati milleti, ati ẹwẹ, fi wọn sinu ikoko kan, ki o si fi wọn ṣe akara, gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ li ẹgbẹ́ rẹ, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ ni iwọ o jẹ ninu rẹ̀. 10 Iwọ o si jẹ onjẹ rẹ nipa ìwọn, ogún ìwọn ṣekeli li ọjọ kan, lati akoko de akoko ni iwọ o jẹ ẹ. 11 Iwọ o si mu omi nipa ìwọn, idamẹfa oṣuwọ̀n hini kan: lati akoko de akoko ni iwọ o mu u. 12 Iwọ o si jẹ ẹ bi akara ọka bàba, iwọ o si fi igbẹ́ enia din i, li oju wọn. 13 Oluwa si wipe, Bayi li awọn ọmọ Israeli yio jẹ akara aimọ́ wọn larin awọn keferi, nibiti emi o le wọn lọ. 14 Nigbana ni mo wipe, A, Oluwa Ọlọrun! kiye si i, a kò ti sọ ọkàn mi di aimọ́: nitori lati igba ewe mi wá titi di isisiyi, emi kò ti ijẹ ninu ohun ti o kú fun ara rẹ̀, tabi ti a faya pẹrẹpẹrẹ, bẹ̃ni ẹran ẽwọ̀ kò iti iwọ̀ mi li ẹnu ri. 15 Nigbana ni o wi fun mi pe, Wõ, mo ti fi ẹlẹbọtọ fun ọ dipò igbẹ́ enia, iwọ o si fi ṣe akara rẹ. 16 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, kiye si i, emi o ṣẹ ọpá onjẹ ni Jerusalemu: nwọn o si jẹ akara nipa ìwọn, ati pẹlu itọju; nwọn o si mu omi nipa ìwọn ati pẹlu iyanu. 17 Ki nwọn ki o le ṣe alaini akara ati omi, ki olukuluku wọn ki o le yanu si ọmọ-nikeji rẹ̀, ki nwọn si run nitori ẹ̀ṣẹ wọn.

Esekieli 5

Esekiẹli Gé Irun Rẹ̀

1 IWỌ, ọmọ enia, mu ọbẹ mimú, mu abẹ onigbajamọ̀, ki o si mu u kọja li ori rẹ, ati ni irùngbọn rẹ: si mu oṣuwọ̀n lati wọ̀n, ki o si pin irun na. 2 Iwọ o si fi iná sun idamẹta li ãrin ilu, nigbati ọjọ didotì ba pé: iwọ o si mu idamẹta, ki o si fi ọbẹ bù u kakiri: idamẹta ni iwọ o si tuka sinu ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn. 3 Iwọ o si mu iye diẹ nibẹ, iwọ o si dì wọn si eti aṣọ rẹ. 4 Si tun mu ninu wọn, ki o si sọ wọn si ãrin iná, ki o si sun wọn ninu iná; lati inu rẹ̀ wá ni iná o ti jade wá si gbogbo ile Israeli. 5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni Jerusalemu: Emi ti gbe e kalẹ li ãrin awọn orilẹ-ède, ati awọn ilẹ ti o wà yi i ka kiri. 6 O si ti pa idajọ mi dà si buburu ju awọn orilẹ-ède lọ, ati ilana mi ju ilẹ ti o yi i kakiri: nitori nwọn ti kọ̀ idajọ ati ilana mi, nwọn kò rìn ninu wọn. 7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Nitori ti ẹnyin ṣe ju awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri lọ, ti ẹnyin kò rìn ninu ilana mi, ti ẹ kò pa idajọ mi mọ, ti ẹ kò si ṣe gẹgẹ bi idajọ awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri. 8 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: kiye si i, Emi, ani Emi, doju kọ ọ, emi o si ṣe idajọ li ãrin rẹ li oju awọn orilẹ-ède. 9 Emi o si ṣe ninu rẹ ohun ti emi kò ṣe ri, iru eyi ti emi kì yio si ṣe mọ, nitori gbogbo ohun irira rẹ. 10 Nitorina awọn baba yio jẹ awọn ọmọ li ãrin rẹ, ati awọn ọmọ yio si jẹ awọn baba wọn; emi o si ṣe idajọ ninu rẹ, ati gbogbo iyokù rẹ li emi o tuka si gbogbo ẹfũfù. 11 Nitorina Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà; Nitõtọ, nitori ti iwọ ti sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́ nipa ohun ẹgbin rẹ, ati pẹlu gbogbo ohun irira rẹ, nitori na li emi o ṣe dín ọ kù, oju mi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ṣãnu fun ọ. 12 Idámẹta rẹ yio kú nipa ajakalẹ arùn, nwọn o si run li ãrin rẹ nipa iyàn, idámẹta yio si ṣubu nipa idà yi ọ ka kiri, emi o si tú idamẹta ká si gbogbo ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn. 13 Bayi ni ibinu mi o ṣẹ, emi o si mu ibinu mi duro lori wọn, inu mi yio si tutù: nwọn o si mọ̀ pe emi Oluwa ti sọ ọ ninu itara mi, nigbati mo ba pari ibinu mi ninu wọn. 14 Emi o si fi ọ ṣòfo, emi o si sọ ọ di ẹ̀gan lãrin awọn orilẹ-ède ti o yi ọ ka kiri, li oju gbogbo awọn ti nkọja. 15 Bẹ̃ni yio si di ẹ̀gan ati ẹsín, ẹkọ́ ati iyanu si awọn orilẹ-ède ti o wà yi ọ ka kiri; nigbati emi o ṣe idajọ ninu rẹ ninu ibinu, ati ninu irunu on ibawi irunu. Emi Oluwa li o sọ ọ. 16 Nigbati emi o rán ọfà buburu iyàn si wọn, eyi ti yio jẹ fun iparun wọn, eyi ti emi o rán lati run nyin: emi o si sọ iyàn di pupọ̀ fun nyin, emi o si ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin. 17 Bẹ̃ni emi o rán iyàn ati ẹranko buburu si nyin, nwọn o si gbà ọ li ọmọ, ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ̀ yio si kọja lãrin rẹ, emi o si mu idà wá sori rẹ. Emi Oluwa li o ti sọ ọ.

Esekieli 6

Ọlọrun fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, kọju rẹ si awọn oke-nla Israeli, si sọtẹlẹ si wọn. 3 Si wipe, Ẹnyin oke-nla Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; bayi li Oluwa Ọlọrun wi si awọn oke-nla, si awọn oke kekeke, si awọn odò siṣàn, ati si awọn afonifoji; kiyesi i, Emi, ani Emi, o mu idà wá sori nyin, emi o si pa ibi giga nyin run. 4 Pẹpẹ nyin yio si di ahoro, ere nyin yio si fọ; okú nyin li emi o si gbe jù siwaju oriṣa nyin. 5 Emi o si tẹ́ okú awọn ọmọ Israeli siwaju oriṣa wọn; emi o si tú egungun nyin ka yi pẹpẹ nyin ka. 6 Ilu-nla li a o parun ninu gbogbo ibugbe nyin, ibi giga yio si di ahoro: ki a le run pẹpẹ nyin, ki a si sọ ọ di ahoro, ki a si le fọ́ oriṣa nyin, ki o si tan, ki a si le ké ere nyin lu ilẹ, ki iṣẹ́ nyin si le parẹ. 7 Okú yio si ṣubu li ãrin nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa. 8 Ṣugbọn emi o fi iyokú silẹ, ki ẹnyin le ni diẹ ti yio bọ́ lọwọ idà lãrin awọn orilẹ-ède, nigbati a o tú nyin ka gbogbo ilẹ. 9 Awọn ti o bọ́ ninu nyin yio si ranti mi, lãrin awọn orilẹ-ède nibiti nwọn o gbe dì wọn ni igbekun lọ, nitoriti mo ti fọ́ ọkàn agbere wọn ti o ti lọ kuro lọdọ mi, ati pẹlu oju wọn, ti nṣagbere lọ sọdọ oriṣa wọn: nwọn o si sú ara wọn nitori ìwa ibi ti nwọn ti hù ninu gbogbo irira wọn. 10 Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, emi kò wi lasan pe, emi o ṣe ibi yi si wọn. 11 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pàtẹwọ rẹ, si fi ẹsẹ rẹ kì ilẹ; si wipe, o ṣe! fun gbogbo irira buburu ilẹ Israeli, nitori nwọn o ṣubu nipa idà, nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ àrun. 12 Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn. 13 Nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati okú wọn yio wà larin ere wọn yi pẹpẹ wọn ka, lori oke kekeke gbogbo, lori ṣonṣo ori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo, ati labẹ gbogbo igi oaku bibò, ibiti nwọn ti rubọ õrùn didùn si gbogbo ere wọn. 14 Bẹ̃ li emi o nà ọwọ́ mi jade sori wọn, emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitotọ, yio di ahoro jù aginju iha Diblati lọ, ninu gbogbo ibugbe wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 7

Òpin ti dé Tán fún Israẹli

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Iwọ ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi pẹlu si ile Israeli; Opin, opin de sori igun mẹrẹrin ilẹ. 3 Opin de si ọ wayi, emi o si rán ibinu mi sori rẹ, emi o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ; emi o si san gbogbo irira rẹ pada si ọ lori. 4 Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ṣugbọn emi o san ọ̀na rẹ pada si ọ lori, ati irira rẹ yio wà li ãrin rẹ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa. 5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; ibi kan, ibi kanṣoṣo, kiye si i, o de. 6 Opin de, opin de: o jí si ọ; kiye si i, o de. 7 Ilẹ mọ́ ọ, iwọ ẹniti ngbe ilẹ na: akokò na de, ọjọ wahala sunmọ tosí; kì isi ṣe ariwo awọn oke-nla. 8 Nisisiyi li emi o dà ikannu mi si ọ lori, emi o si mu ibinu mi ṣẹ si ọ lori: emi o si dá ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, emi o si san fun ọ nitori gbogbo irira rẹ. 9 Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: emi o si san fun ọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati irira rẹ ti mbẹ lãrin rẹ; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa ti nkọlu. 10 Kiye si i ọjọ na, kiyesi i, o de: ilẹ ti mọ́; ọpá ti tanná, irera ti rudi. 11 Iwa-ipa ti dide di ọpa ìwa buburu: ọkan ninu wọn kì yio kù, tabi ninu ọ̀pọlọpọ wọn, tabi ninu ohun kan wọn, bẹ̃ni kì yio si ipohùnreré ẹkun fun wọn. 12 Akoko na de, ọjọ na sunmọ itosi: ki olùra máṣe yọ̀, bẹ̃ni ki olùta máṣe gbãwẹ: nitori ibinu de ba gbogbo wọn. 13 Nitori olùta kì yio pada si eyi ti a tà, bi wọn tilẹ wà lãye: nitori iran na kàn gbogbo enia ibẹ̀, ti kì yio pada; bẹ̃ni kò si ẹniti yio mu ara rẹ̀ le ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 14 Nwọn ti fọn ipè, lati jẹ ki gbogbo wọn mura; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o lọ si ogun: nitori ibinu mi wà lori gbogbo wọn. 15 Idà mbẹ lode, ajakálẹ àrun ati iyàn si mbẹ ninu: ẹniti o wà li oko yio kú nipa idà; ẹniti o wà ninu ilu, iyàn ati ajakálẹ àrun ni yio si jẹ ẹ run. 16 Ṣugbọn awọn ti o bọ́ ninu wọn yio salà, nwọn o si wà lori oke bi adabà afonifoji, gbogbo nwọn o ma gbãwẹ, olukuluku nitori aiṣedede rẹ̀. 17 Gbogbo ọwọ́ ni yio rọ, gbogbo ẽkun ni yio si di ailera bi omi. 18 Aṣọ ọ̀fọ ni nwọn o fi gbajá pẹlu; ìbẹru ikú yio si bò wọn mọlẹ; itiju yio si wà loju gbogbo wọn, ẽpá yio si wà li ori gbogbo wọn. 19 Nwọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn li a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yio si le gbà wọn là li ọjọ ibinu Oluwa: nwọn kì yio tẹ́ ọkàn wọn lọrùn, bẹ̃ni nwọn kì yio kún inu wọn; nitori on ni idùgbolu aiṣedede wọn. 20 Bi o ṣe ti ẹwà ohun ọṣọ́ rẹ̀ ni, o gbe e ka ibi ọlanla: ṣugbọn nwọn yá ere irira wọn ati ohun ikorira wọn ninu rẹ̀: nitorina li emi ṣe mu u jina si wọn. 21 Emi o si fi i si ọwọ́ awọn alejo fun ijẹ, ati fun enia buburu aiye fun ikogun: nwọn o si bà a jẹ. 22 Oju mi pẹlu li emi o yipada kuro lọdọ wọn, nwọn o si ba ibi ikọkọ mi jẹ; nitori awọn ọlọṣà yio wọ inu rẹ̀, nwọn o si bà a jẹ. 23 Rọ ẹ̀wọn kan; nitori ilẹ na kún fun ẹ̀ṣẹ ẹjẹ, ilu-nla na si kún fun iwa ipa. 24 Nitorina li emi o mu awọn keferi ti o burujulọ, nwọn o si jogun ile wọn: emi o si mu ọṣọ-nla awọn alagbara tán pẹlu, ibi mimọ́ wọn li a o si bajẹ. 25 Iparun mbọ̀ wá, nwọn o si wá alafia, kì yio si si. 26 Tulasì yio gori tulasi, irọkẹ̀kẹ yio si gori irọkẹ̀kẹ; nigbana ni nwọn o bere lọdọ woli; ṣugbọn ofin yio ṣegbé kuro lọdọ alufa, ati imọ̀ kuro lọdọ awọn agbà. 27 Ọba yio ṣọ̀fọ, a o si fi idahoro wọ̀ ọmọ-alade, ọwọ́ awọn enia ilẹ na li a o wahala, emi o ṣe si wọn gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi ẹjọ wọn ti ri li emi o dá a fun wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 8

Ìwà Ìbọ̀rìṣà Ní Jerusalẹmu

1 O si ṣe, li ọdun ẹkẹfa, li oṣù ẹkẹfa, li ọjọ karun oṣù, bi mo ti joko ni ile mi, ti awọn àgbagba Juda si joko niwaju mi, ni ọwọ́ Oluwa Ọlọrun bà le mi nibẹ. 2 Nigbana ni mo wò, si kiye si i, aworán bi irí iná: lati irí ẹgbẹ rẹ̀ ani de isalẹ, iná; ati lati ẹgbẹ́ rẹ de oke, bi irí didan bi àwọ amberi. 3 O si nà àworan ọwọ́ jade, o si mu mi ni ìdi-irun ori mi; ẹmi si gbe mi soke lagbedemeji aiye on ọrun, o si mu mi wá ni iran Ọlọrun si Jerusalemu, si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ti inu to kọju si ariwa; nibiti ijoko ere owu wà ti nmu ni jowu. 4 Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wà nibẹ, gẹgẹ bi iran ti mo ri ni pẹtẹlẹ. 5 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gbe oju rẹ soke nisisiyi si ọ̀na ihà ariwa. Bẹ̃ni mo gbe oju mi soke si ọ̀na ihà ariwa, si kiye si i, ere owu yi niha ariwa li ati-wọle ọ̀na pẹpẹ. 6 Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, iwọ ri ohun ti nwọn nṣe? ani irira nla ti ile Israeli nṣe nihinyi, ki emi ba le lọ jina kuro ni ibi mimọ́ mi? ṣugbọn si tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o jù wọnyi lọ. 7 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na agbala; nigbati mo si wò, kiye si i iho lara ogiri. 8 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, dá ogirí na lu nisisiyi: nigbati mo si ti dá ogiri na lu tan, kiye si i, ilẹkun. 9 O si wi fun mi pe, Wọ ile, ki o si wo ohun irira buburu ti nwọn nṣe nihin. 10 Bẹ̃ni mo wọle, mo si ri; si kiye si i, gbogbo aworan ohun ti nrakò, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israeli li a yá li aworan lara ogiri yika kiri. 11 Adọrin ọkunrin ninu awọn agbà ile Israeli si duro niwaju wọn, Jaasania ọmọ Ṣafani si duro lãrin wọn, olukuluku pẹlu awo turari lọwọ rẹ̀; ẹ̃fin ṣiṣu dùdu ti turari si goke lọ. 12 Nigbana li o si wi fun mi pe, Ọmọ enia iwọ ri ohun ti awọn agbà ile Israeli nṣe li okunkùn, olukuluku ninu iyará oriṣa tirẹ̀? nitori nwọn wipe, Oluwa kò ri wa; Oluwa ti kọ̀ aiye silẹ. 13 O si wi fun mi pe, Tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi jù yi ti nwọn nṣe. 14 Nigbana li o mu mi wá si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ti o wà nihà ariwa; si kiye si i, awọn obinrin joko nwọn nsọkun fun Tammusi. 15 Nigbana li o sọ fun mi pe, Iwọ ri eyi, Iwọ ọmọ enia? tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi ju wọnyi lọ. 16 O si mu mi wá si inu agbala ile Oluwa, si kiye si i, li ẹnu-ọ̀na tempili Oluwa, lãrin iloro ati pẹpẹ, ni iwọ̀n ọkunrin mẹ̃dọgbọ̀n wà, ti nwọn kẹ̀hin si tẹmpili Oluwa, ti nwọn si kọju si ila-õrùn; nwọn si foribalẹ fun õrun si ila-õrun. 17 Nigbana li o wi fun mi pe, Iwọ ri eyi, ọmọ enia? ohun kekere ni fun ile Juda lati ṣe ohun irira ti nwọn nṣe nihin? nitori nwọn fi ìwa-ipa kún ilẹ na, nwọn si ti pada lati mu mi binu, si kiye si i, nwọn tẹ̀ ẹka-igi bọ imú wọn. 18 Emi pẹlu yio si fi irúnu ba wọn lò: oju mi kì yio dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ati bi o tilẹ ṣepe nwọn fi ohùn rara kigbe li eti mi, sibẹ emi kì yio gbọ́ ti wọn.

Esekieli 9

Wọ́n Jẹ Jerusalẹmu Níyà

1 O si fi ohùn rara kigbe li eti mi wipe, Mu gbogbo awọn alaṣẹ ilu sunmọ itosi, olukuluku ton ti ohun ija iparun li ọwọ́ rẹ̀. 2 Si kiyesi i, ọkunrin mẹfa jade lati ẹnu ilẹkun oke wá, ti o wà niha ariwa, olukuluku ton ti ohun-ijà ipani li ọwọ́ rẹ̀: ọkunrin kan ninu wọn si wọ aṣọ ọgbọ̀, pẹlu ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: nwọn si wọ inu ile, nwọn si duro lẹba pẹpẹ idẹ. 3 Ogo Ọlọrun Israeli si ti goke kuro lori kerubu, eyi ti o ti wà, si iloro ile. O si pe ọkunrin na ti o wọ aṣọ ọgbọ̀, ti o ni ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: 4 Oluwa si wi fun u pe, La ãrin ilu já, li ãrin Jerusalemu, ki o si sami si iwaju awọn ọkunrin ti nkẹdùn, ti nwọn si nkigbe nitori ohun irira ti nwọn nṣe lãrin rẹ̀. 5 O si sọ fun awọn iyokù li eti mi, pe, Ẹ tẹ̀ le e la ilu lọ, ẹ si ma kọlù: ẹ má jẹ ki oju nyin dasi, bẹ̃ni ẹ máṣe ṣãnu. 6 Ẹ pa arugbo ati ọmọde patapata, awọn wundia ati ọmọ kekeke ati obinrin; ṣugbọn ẹ máṣe sunmọ ẹnikan lara ẹniti àmi na wà; ẹ si bẹrẹ lati ibi mimọ́ mi. Bẹ̃ni nwọn bẹrẹ lati ọdọ awọn agbà ti o wà niwaju ile. 7 O si wi fun wọn pe, ẹ sọ ile na di aimọ́, ẹ si fi okú kún agbala na: ẹ jade lọ. Nwọn si jade lọ, nwọn si pa enia ni ilu. 8 O si ṣe, nigbati nwọn npa wọn, ti a si fi emi silẹ, mo da oju mi bo ilẹ, mo si kigbe, mo si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha pa gbogbo awọn iyokù Israeli run, nipa dida irúnu rẹ jade sori Jerusalemu? 9 O si wi fun mi pe, Aiṣedede ile Israeli ati ti Juda pọ̀ gidigidi, ilẹ na si kún fun ẹjẹ, ilu si kún fun iyi-ẹjọ-po, nitori nwọn wipe, Oluwa ti kọ aiye silẹ, Oluwa kò riran. 10 Bi o si ṣe ti emi ni, oju mi kì o dasi, bẹ̃li emi kì o ṣanu, ṣugbọn emi o sán ọ̀na wọn pada si ori wọn. 11 Si kiye si i, ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, ti o ni ìwo-tadawa li ẹgbẹ́ rẹ̀ rohìn, wipe, mo ti ṣe gẹgẹ bi o ti paṣẹ fun mi.

Esekieli 10

Ògo OLUWA Kúrò Ninu Tẹmpili Náà

1 MO si wò, si kiye si i, ninu ofurufu ti o wà loke lori awọn kerubu, ohun kan hàn li ori wọn bi okuta safire bi irí aworan itẹ́. 2 O si sọ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, o si wipe, Bọ sarin kẹkẹ, labẹ kerubu; si bu ikúnwọ ẹyin iná lati agbedemeji awọn kerubu; si fọ́n wọn ka sori ilu na. O si wọ inu ile li oju mi. 3 Awọn kerubu si duro li apá ọtun ile na, nigbati ọkunrin na wọ ile; awọ sanma si kún agbala ti inu. 4 Ogo Oluwa si goke lọ kuro lori kerubu o si duro loke iloro ile na; ile na si kún fun awọsanma, agbala na si kùn fun didán ogo Oluwa. 5 A si gbọ́ iró iyẹ awọn kerubu titi de agbala ode, bi ohùn Ọlọrun Oludumare nigbati o nsọ̀rọ. 6 O si ṣe, nigbati o ti paṣẹ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọgbọ, wipe, Fọn iná lati ãrin awọn kẹkẹ, lati ãrin awọn kerubu, o si wọ inu ile, o si duro lẹba awọn kẹkẹ. 7 Kerubu kan si nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati ãrin awọn kerubu si iná ti o wà li ãrin awọn kerubu, o si mu ninu rẹ̀, o si fi si ọwọ́ ẹniti o wọ aṣọ ọgbọ̀: ẹniti o gbà a; ti o si jade lọ. 8 Aworan ọwọ́ enia si hàn ninu awọn kerubu labẹ iyẹ́ wọn. 9 Nigbati mo si wò, kiye si i, awọn kẹkẹ mẹrin na niha awọn kerubu, kẹkẹ kan niha kerubu kan, ati kẹkẹ miran niha kerubu miran; irí awọn kẹkẹ na si dabi awọ̀ okuta berili. 10 Bi o si ṣe ti irí wọn, awọn mẹrẹrin ni aworan kanna, bi ẹnipe kẹkẹ́ kan ti wà li ãrin kẹkẹ́ kan. 11 Nigbati nwọn lọ, nwọn fi ihà wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò yipada bi nwọn ti nlọ, ṣugbọn ibi ti ori ba kọju si, nwọn a tẹle e; nwọn kò yipada bi nwọn ti nlọ. 12 Ati gbogbo ara wọn, ati ẹhìn wọn, ati ọwọ́ wọn ati iyẹ́ wọn, ati awọn kẹkẹ́, kún fun oju yika kiri kẹkẹ́, ti awọn mẹrẹrin ni. 13 Niti awọn kẹkẹ́, a ke si wọn li etí mi wipe, Kẹkẹ́! 14 Olukuluku wọn si ni oju mẹrin, oju ekini oju kerubu, oju keji, oju enia, ati ẹkẹta oju kiniun, ati ẹkẹrin oju idi. 15 A si gbe awọn kerubu soke, eyi ni ẹda alãye ti mo ri lẹba odò Kebari. 16 Nigbati awọn kerubu si lọ, awọn kẹkẹ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke lati fò soke kuro lori ilẹ, kẹkẹ́ kanna kò yipada kuro li ẹgbẹ́ wọn. 17 Nigbati nwọn duro, wọnyi duro; nigbati a si gbe wọn soke, wọnyi gbe ara wọn soke pẹlu; nitori ẹmi ẹda alãye na mbẹ ninu wọn. 18 Ogo Oluwa si lọ kuro ni iloro ile na, o si duro lori awọn kerubu. 19 Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, nwọn si fò kuro lori ilẹ li oju mi: nigbati nwọn jade lọ, awọn kẹkẹ wà li ẹgbẹ̀ wọn pẹlu, olukuluku si duro nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ilà-õrun ile Oluwa: ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke. 20 Eyi ni ẹda alãye ti mo ri labẹ Ọlọrun Israeli li ẹba odò Kebari, mo si mọ̀ pe kerubu ni nwọn. 21 Olukuluku wọn ni oju mẹrin li ọkankan, olukuluku wọn si ni iyẹ́ mẹrin; ati aworan ọwọ́ enia wà li abẹ iyẹ́ wọn. 22 Aworan oju wọn si jẹ oju kanna ti mo ri lẹba odò Kebari, iri wọn ati awọn tikara wọn: olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran.

Esekieli 11

1 ẸMI si gbe mi soke, o si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa ti ilà õrun ti o kọju siha ilà-õrùn, si kiyesi i, ọkunrin mẹdọgbọn wà nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na; ninu awọn ẹniti mo ri Jaasania ọmọ Assuri, ati Pelatia ọmọ Benaia, awọn ijoyè awọn enia. 2 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, awọn ọkunrin ti npete ikà ni wọnyi, ti nsi gbimọ̀ buburu ni ilu yi: 3 Awọn ti o wipe, Kò sunmọ tosi; ẹ jẹ ki a kọ ile: ilu yi ni ìgba, awa si ni ẹran. 4 Nitorina sọtẹlẹ si wọn, Ọmọ enia, sọtẹlẹ. 5 Ẹmi Oluwa si bà le mi, o si wi fun mi pe, Sọ̀rọ; Bayi li Oluwa wi; Bayi li ẹnyin ti wi, Ile Israeli, nitoriti mo mọ̀ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin. 6 Ẹnyin ti sọ okú nyin di pupọ̀ ni ilu yi, ẹnyin si ti fi okú kún igboro rẹ̀, 7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Awọn okú nyin ti ẹnyin ti tẹ́ si ãrin rẹ̀, awọn ni ẹran, ilu yi si ni ìgba; ṣugbọn emi o mu nyin jade kuro lãrin rẹ̀. 8 Oluwa Ọlọrun wipe, Ẹnyin ti bẹ̀ru idà, emi o si mu idà wa sori nyin. 9 Emi o si mu nyin kuro lãrin rẹ̀, emi o si fi nyin le awọn alejo lọwọ, emi o si mu idajọ ṣẹ si nyin lara. 10 Nipa idà li ẹnyin o ṣubu; emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 11 Ilu yi ki yio ṣe ìgba fun nyin, bẹ̃ni ẹnyin kì yio jẹ ẹran lãrin rẹ̀; ṣugbọn emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli. 12 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitoriti ẹnyin kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni ẹnyin kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn ẹnyin ti hu ìwa awọn keferi ti o wà yi nyin ka. 13 O si ṣe, nigbati mo sọtẹlẹ, Pelatia ọmọ Benaiah kú. Mo si dojubolẹ, mo si fi ohùn rara kigbe, mo si wipe, A! Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha ṣe aṣetan iyokù Israeli bi? 14 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 15 Ọmọ enia, awọn ará rẹ, ani awọn ará rẹ, awọn ọkunrin ninu ibatan rẹ, ati gbogbo ile Israeli patapata, ni awọn ti awọn ara Jerusalemu ti wi fun pe, Ẹ jina si Oluwa; awa ni a fi ilẹ yi fun ni ini. 16 Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Bi mo tilẹ ti tá wọn nù réré lãrin awọn keferi; bi mo si ti tú wọn ka lãrin ilẹ pupọ, sibẹ emi o jẹ ibi mimọ́ kekere fun wọn ni ilẹ ti wọn o de. 17 Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Emi tilẹ kó nyin kuro lọdọ awọn orilẹ-ède; emi o si kó nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ká si, emi o si fun nyin ni ilẹ Israeli. 18 Nwọn o si wá sibẹ, nwọn o si mu gbogbo ohun irira rẹ̀ ati gbogbo ohun ẽri rẹ̀ kuro nibẹ. 19 Emi o si fun wọn li ọkàn kan, emi o si fi ẹmi titun sinu nyin; emi o si mu ọkàn okuta kuro lara wọn, emi o si fun wọn li ọkàn ẹran: 20 Ki wọn le rìn ninu aṣẹ mi, ki wọn si le pa ilana mi mọ, ki nwọn si ṣe wọn: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn. 21 Ṣugbọn bi o ṣe ti awọn ti ọkàn wọn nrìn nipa ọkàn ohun irira ati ohun ẽri wọn, Emi o sẹsan ọ̀na wọn sori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi. 22 Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, pelu awọn kẹkẹ́ lẹgbẹ wọn, ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke. 23 Ogo Oluwa si goke lọ kuro lãrin ilu na; o si duro lori oke-nla, ti o wà nihà ila-õrùn ilu na. 24 Lẹhin na ẹmi gbe mi soke, o si mu mi wá si Kaldea li ojuran, nipa Ẹmi Ọlọrun sọdọ awọn ti igbekun. Bẹ̃ni iran ti mo ti ri lọ kuro lọdọ mi. 25 Mo si sọ gbogbo ohun ti Oluwa ti fi hàn mi fun awọn ti igbekùn.

Esekieli 12

Wolii Gẹ́gẹ́ Bí Ẹni Tí Ó sá fógun

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, iwọ ngbe ãrin ọlọ̀tẹ ile, ti nwọn ni oju lati ri, ti kò si ri; nwọn ni eti lati gbọ́, nwọn kò si gbọ́: nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn. 3 Nitorina, iwọ ọmọ enia, mura nkan kikolọ, ki o si kó lọ li oju wọn li ọsan; ki o si kó lati ipò rẹ lọ si ibomiran li oju wọn; o le ṣe pe nwọn o ronu, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile. 4 Ki o si mu nkan rẹ jade li ọsan li oju wọn, bi nkan kikolọ; ki o si jade lọ li aṣalẹ li oju wọn, bi awọn ti nlọ si igbekùn. 5 Da ogiri lu loju wọn, ki o si kó jade nibẹ. 6 Li oju wọn ni ki o rù u le ejika rẹ, ki o si rù u lọ ni wiriwiri alẹ, ki o si bo oju rẹ, ki o má ba ri ilẹ; nitori mo ti gbe ọ kalẹ fun àmi si ile Israeli. 7 Mo si ṣe bi a ti paṣẹ fun mi: mo mu nkan mi jade li ọsan, bi nkan fun igbekùn, mo si fi ọwọ́ mi dá ogiri lu li aṣalẹ; mo gbe e jade ni wiriwiri alẹ, mo si rù u le ejika mi loju wọn. 8 Li owurọ ọ̀rọ Oluwa si ti tọ̀ mi wá, wipe, 9 Ọmọ enia, ile Israeli, ọlọ̀tẹ ile nì kò ti wi fun ọ pe, kini iwọ nṣe? 10 Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹrù yi hàn fun awọn ọmọ-alade ni Jerusalemu, ati gbogbo ile Israeli ti o wà lãrin wọn. 11 Wipe, emi ni àmi nyin, gẹgẹ bi mo ti ṣe, bẹ̃ni a o si ṣe si wọn: nwọn o ko kuro, nwọn o si lọ si igbekùn. 12 Ọmọ-alade ti o wà larin wọn yio si rẹrù lori ejika rẹ̀ ni wiriwiri alẹ, yio si jade lọ; nwọn o si dá ogiri lu lati kó jade nibẹ; yio si bo oju rẹ̀, ki o má ba fi oju rẹ̀ ri ilẹ. 13 Awọ̀n mi ni emi o si tẹ́ le e lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi: emi o si mu u wá si Babiloni, si ilẹ awọn ara Kaldea; kì yio si ri i, bẹ̃ni yio kú nibẹ. 14 Gbogbo awọn ti o yi i ka lati ràn a lọwọ, ati gbogbo ọwọ-ogun rẹ̀, ni emi o tuká si gbogbo afẹ̃fẹ, emi o si yọ idà le wọn. 15 Nwọn o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa, nigbati mo ba tú wọn ka lãrin awọn orilẹ-ède; ti mo ba si fọ́n wọn ká ilẹ pupọ. 16 Ṣugbọn emi o kù diẹ ninu wọn silẹ lọwọ idà, lọwọ iyàn, ati lọwọ ajakálẹ arùn; ki nwọn le sọ gbogbo ohun ẽri wọn lãrin awọn keferi, nibiti nwọn ba de; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 17 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 18 Ọmọ enia, fi ìgbọnriri jẹ onjẹ rẹ, si fi ìwariri ati ikiyesara mu omi rẹ; 19 Ki o si sọ fun awọn enia ilẹ na pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn ara Jerusalemu, niti ilẹ Israeli; nwọn o fi ikiyesara jẹ onjẹ wọn, nwọn o si fi iyanu mu omi wọn, ki ilẹ rẹ̀ ki o le di ahoro kuro ninu gbogbo ohun ti o wà ninu rẹ̀, nitori ìwa-ipá gbogbo awọn ti ngbe ibẹ̀. 20 Awọn ilu ti a ngbe yio di ofo, ilẹ na yio si di ahoro; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 21 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 22 Ọmọ enia, owe wo li ẹnyin ni, ni ilẹ Israeli pe, A fà ọjọ gùn, gbogbo iran di asan? 23 Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o jẹ ki owe yi dẹkun, nwọn kì yio si pa a li owe ni Israeli mọ; ṣugbọn wi fun wọn pe, Ọjọ kù si dẹ̀dẹ; ati imuṣẹ gbogbo iran. 24 Nitori kì yio si iran asan mọ, kì yio si si afọṣẹ ti npọnni ninu ile Israeli. 25 Nitori emi li Oluwa: emi o sọ̀rọ, ọ̀rọ ti emi o sọ yio si ṣẹ, a kì yio fà a gùn mọ; nitori li ọjọ nyin, Ọlọtẹ ile, li emi o sọ ọ̀rọ na, emi o si ṣe e, ni Oluwa Ọlọrun wi. 26 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, 27 Ọmọ enia, kiyesi i, awọn ara ile Israeli wipe, Iran ti o ri, fun ọjọ pupọ ti mbọ̀ ni, o si sọ asọtẹlẹ akoko ti o jina rere. 28 Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Kò si ọkan ninu ọ̀rọ mi ti a o fà gùn mọ, ṣugbọn ọ̀rọ ti mo ti sọ yio ṣẹ, ni Oluwa wi.

Esekieli 13

Ìran Ibi Nípa Àwọn Ọkunrin Wolii Èké

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe: 2 Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn woli Israeli ti nsọtẹlẹ, ki o si wi fun awọn ti nti ọkàn ara wọn sọtẹlẹ pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; 3 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, egbé ni fun awọn aṣiwere woli, ti nwọn ntẹ̀le ẹmi ara wọn, ti wọn kò si ri nkan! 4 Israeli, awọn woli rẹ dabi kọ̀lọkọ̀lọ ni ijù, 5 Ẹnyin kò ti goke lọ si ibi ti o ya, bẹ̃ni ẹ kò si tun odi mọ fun ile Israeli lati duro li oju ogun li ọjọ Oluwa. 6 Nwọn ti ri asan ati àfọṣẹ eke, pe, Oluwa wi: bẹ̃ni Oluwa kò rán wọn, nwọn si ti jẹ ki awọn ẹlomiran ni ireti pe, nwọn o fi idí ọ̀rọ wọn mulẹ. 7 Ẹnyin kò ti ri iran asan, ẹ kò si ti fọ àfọṣẹ eke, ti ẹnyin wipe, Oluwa wi bẹ̃? bẹ̃ni emi kò sọrọ. 8 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ẹnyin ti sọ̀rọ asan, ẹnyin si ti ri eke, nitorina, kiyesi i, mo dojukọ nyin, ni Oluwa wi. 9 Ọwọ́ mi yio si wà lori awọn woli, ti nwọn ri asan, ti nwọn si nfọ àfọṣẹ eke; nwọn kì yio si ninu ijọ awọn enia mi, bẹ̃ni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israeli; bẹ̃ni nwọn kì yio wọ̀ ilẹ Israeli, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 10 Nitori, ani nitori ti nwọn ti tàn awọn enia mi wipe, Alafia; bẹ̃ni kò si alafia, ọkan si mọ ogiri, si kiyesi, awọn miran si nfi amọ̀ ti a kò pò rẹ́ ẹ. 11 Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a. 12 Kiyesi i, nigbati ogiri na ba wo, a kì yio ha wi fun nyin pe, Rirẹ́ ti ẹnyin rẹ́ ẹ ha dà? 13 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o tilẹ fi ẹfũfu lile ya a ni irúnu mi; òjo yio si rọ̀ pupọ ni ibinu mi, ati yinyin nla ni irúnu mi lati run u. 14 Bẹ̃ni emi o wo ogiri ti ẹnyin fi amọ̀ aipò rẹ́ lulẹ, emi o si mu u wá ilẹ, tobẹ̃ ti ipilẹ rẹ̀ yio hàn, yio si ṣubu, a o si run nyin li ãrin rẹ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa. 15 Bayi li emi o mu ibinu mi ṣẹ lori ogiri na, ati lori awọn ti o fi amọ̀ aipò rẹ ẹ, emi o si wi fun nyin pe, Ogiri na kò si mọ ati awọn ti o ti rẹ́ ẹ; 16 Eyini ni, awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ niti Jerusalemu, ti nwọn si ri iran alafia fun u, bẹ̃ni alafia kò si, ni Oluwa Ọlọrun wi. 17 Iwọ ọmọ enia, dojukọ awọn ọmọbinrin awọn enia rẹ bẹ̃ gẹgẹ, ti nwọn nsọtẹlẹ lati ọkàn ara wọn wá; ki o si sọtẹlẹ si wọn. 18 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Egbé ni fun awọn obinrin ti nrán tìmtim si gbogbo ìgbọnwọ, ti nwọn sì ndá gèle si ori olukuluku enia lati ṣọdẹ ọkàn! Ẹnyin o ṣọdẹ ọkàn awọn enia mi bi, ẹnyin o si gbà ọkàn ti o tọ̀ nyin wá là bi? 19 Ẹnyin o ha si bà mi jẹ lãrin awọn enia mi nitori ikunwọ ọkà bàba, ati nitori òkele onjẹ, lati pa ọkàn ti kì ba kú, ati lati gba awọn ọkàn ti kì ba wà lãye là, nipa ṣiṣeke fun awọn enia mi ti ngbọ́ eke nyin? 20 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ awọn tìmtim nyin, ti ẹnyin fi nṣọdẹ ọkàn nibẹ lati mu wọn fò, emi o si yà wọn kuro li apá nyin, emi o si jẹ ki awọn ọkàn na lọ, ani awọn ọkàn ti ẹnyin ndọdẹ lati mu fò. 21 Gèle nyin pẹlu li emi o ya, emi o si gba awọn enia mi lọwọ nyin, nwọn kì yio si si lọwọ nyin mọ lati ma dọdẹ wọn; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 22 Nitoripe eke li ẹnyin fi mu ọkàn awọn olododo kãnu, awọn ẹniti emi kò mu kãnu, ẹnyin si mu ọwọ́ enia buburu le, ki o má ba pada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀ nipa ṣiṣe ileri ìye fun u: 23 Nitorina ẹnyin kì yio ri asan mọ, ẹ kì yio si ma fọ àfọṣẹ, nitoriti emi o gba awọn enia mi kuro li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 14

Ọlọrun Fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún

1 AWỌN kan ninu awọn àgba Israeli si wá sọdọ mi, nwọn si joko niwaju mi. 2 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 3 Ọmọ enia, awọn ọkunrin wọnyi ti gbe oriṣa wọn si ọkàn wọn, nwọn si fi ohun ìdigbolu aiṣedede wọn siwaju wọn: emi o ha jẹ ki nwọn bere lọwọ mi rara bi? 4 Nitorina sọ fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; olukuluku ọkunrin ile Israeli ti o gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si wá sọdọ woli; emi Oluwa yio dá ẹniti o wá lohùn gẹgẹ bi ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀. 5 Ki emi ba le mu ile Israeli li ọkàn ara wọn, nitori gbogbo wọn di ajeji si mi nipasẹ oriṣa wọn. 6 Nitorina wi fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ ronupiwada, ki ẹ si yipada kuro lọdọ oriṣa nyin, ki ẹ si yi oju nyin kuro ninu ohun ẽri nyin. 7 Nitori olukuluku ninu ile Israeli, tabi ninu alejo ti o ṣe atipo ni Israeli, ti o yà ara rẹ̀ kuro lọdọ mi, ti o si gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si tọ̀ wolĩ kan wá lati bere lọwọ rẹ̀ niti emi: Emi Oluwa yio da a lohùn tikalami: 8 Emi o si dojukọ ọkunrin na, emi o si fi i ṣe àmi ati owe, emi o si ké e kuro lãrin awọn enia mi; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa. 9 Bi a ba si tan wolĩ na jẹ nigbati o sọ ohun kan, Emi Oluwa ni mo ti tan wolĩ na jẹ, emi o si nawọ mi le e, emi o si run u kuro lãrin Israeli enia mi. 10 Awọn ni yio si rù ìya aiṣedẽde wọn; ìya wolĩ na yio ri gẹgẹ bi ìya ẹniti o bẽre lọdọ rẹ̀. 11 Ki ile Israeli má ba ṣako lọ kuro lọdọ mi mọ, ki nwọn má ba fi gbogbo irekọja wọn bà ara wọn jẹ mọ, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ki emi si le jẹ Ọlọrun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi. 12 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, 13 Ọmọ enia, nigbati ilẹ na ba ṣẹ̀ si mi nipa irekọja buburu, nigbana ni emi o nawọ mi le e, emi o si ṣẹ́ ọpa onjẹ inu rẹ̀, emi o si rán ìyan si i, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀: 14 Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi. 15 Bi mo ba jẹ ki ẹranko buburu kọja lãrin ilẹ na, ti nwọn si bà a jẹ, tobẹ̃ ti o di ahoro, ti ẹnikan kò le là a ja nitori awọn ẹranko na. 16 Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gbà ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; awọn nikan li a o gbàla, ṣugbọn ilẹ na yio di ahoro. 17 Tabi bi mo mu idà wá sori ilẹ na, ti mo si wipe, Idà, la ilẹ na ja; tobẹ̃ ti mo ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀: 18 Bi awọn ọkunrin mẹta yi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là, ṣugbọn awọn tikara wọn nikan li a o gbàla. 19 Tabi bi mo rán ajàkalẹ arùn si ilẹ na, ti mo si da irúnu mi le e ni ẹjẹ, lati ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀: 20 Bi Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; kìki ọkàn ara wọn ni awọn o fi ododo wọn gbàla. 21 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Melomelo ni nigbati mo ba rán awọn idajọ kikan mi mẹrẹrin sori Jerusalemu, idà, ati iyàn, ati ẹranko buburu, ati ajakalẹ àrun, lati ké enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀? 22 Ṣugbọn kiye si i, ninu rẹ̀ li a o kù awọn ti a o yọ silẹ, ti a o mu jade wá, ati ọmọkunrin, ati ọmọbinrin, kiye si i, nwọn o jade tọ̀ nyin wá, ẹnyin o si ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn, a o si tù nyin ninu niti ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ani niti gbogbo ohun ti mo ti mu wá sori rẹ̀. 23 Nwọn o si tù nyin ninu, nigbati ẹnyin ba ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe emi kò ṣe gbogbo ohun ti mo ti ṣe ninu rẹ̀ li ainidi, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 15

Òwe Nípa Igi Àjàrà

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, kini igi ajara fi ju igikigi lọ, tabi ju ẹka ti o wà lãrin igi igbo? 3 A ha le mu igi lara rẹ̀ ṣe iṣẹkiṣẹ? tabi enia le mu ẽkàn lara rẹ̀ lati fi ohunkohun kọ́ sori rẹ̀. 4 Kiyesi i, a jù u sinu iná bi igi, iná si jo ipẹkun rẹ̀ mejeji, ãrin rẹ̀ si jona. O ha yẹ fun iṣẹkiṣẹ bi? 5 Kiyesi i, nigbati o wà li odidi, kò yẹ fun iṣẹ kan: melomelo ni kì yio si yẹ fun iṣẹkiṣẹ, nigbati iná ba ti jo o, ti o si jona? 6 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi igi ajara lãrin igi igbó, ti mo ti fi fun iná bi igi, bẹ̃ni emi o fi ara Jerusalemu ṣe. 7 Emi o si doju mi kọ wọn, nwọn o jade kuro ninu iná kan, iná miran yio si jo wọn, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba dojukọ wọn. 8 Emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 16

1 Ọ̀RỌ Oluwa tún tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, jẹ ki Jerusalemu mọ̀ ohun irira rẹ̀. 3 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Jerusalemu; Ibi rẹ ati ilẹ ibi rẹ ni ati ilẹ Kenaani wá; ará Amori ni baba rẹ, ará Hiti si ni iyá rẹ. 4 Ati niti ìbi rẹ, a kò da ọ ni iwọ́ ni ijọ ti a bi ọ, bẹ̃ni a kò wẹ̀ ọ ninu omi lati mu ọ mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ lara rara, bẹ̃ni a kò fi ọja wé ọ rara. 5 Kò si oju ti o kãnu fun ọ, lati ṣe ọkan ninu nkan wọnyi fun ọ, lati ṣe iyọnu si ọ; ṣugbọn ninu igbẹ li a gbe ọ sọ si, fun ikorira ara rẹ, ni ijọ ti a bi ọ. 6 Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si ri ọ, ti a tẹ̀ ọ mọlẹ ninu ẹjẹ ara rẹ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè: nitõtọ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè. 7 Emi ti mu ọ bi si i bi irudi itàna ìgbẹ; iwọ si ti pọ̀ si i, o si ti di nla, iwọ si gbà ohun ọṣọ́ ti o ti inu ọṣọ́ wá: a ṣe ọmú rẹ yọ, irun rẹ si dagba, nigbati o jẹ pe iwọ ti wà nihoho ti o si wà goloto. 8 Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si wò ọ; kiye si i, ìgba rẹ jẹ ìgba ifẹ; mo si nà aṣọ mi bò ọ, mo si bo ihoho rẹ: nitõtọ, mo bura fun ọ, mo si ba ọ da majẹmu, ni Oluwa Ọlọrun wi, iwọ si di temi. 9 Nigbana ni mo fi omi wẹ̀ ọ; nitõtọ, mo wẹ ẹjẹ rẹ kuro lara rẹ patapata, mo si fi ororo kùn ọ lara. 10 Mo wọ̀ ọ laṣọ oniṣẹ-ọnà pẹlu, mo si fi awọ̀ badgeri wọ̀ ọ ni bàta, mo si fi aṣọ ọ̀gbọ daradara di ọ ni amure yika, mo si fi aṣọ ṣẹ́dà bò ọ. 11 Mo fi ohun-ọṣọ ṣe ọ lọṣọ pẹlu, mo si fi júfu bọ̀ ọ lọwọ, mo si fi ẹ̀wọn kọ́ ọ li ọrùn. 12 Mo si fi oruka si ọ ni imú, mo si fi oruka bọ̀ ọ leti, mo si fi ade daradara de ọ lori. 13 Bayi ni a fi wura ati fadaka ṣe ọ lọṣọ; aṣọ rẹ si jẹ ọgbọ̀ daradara, ati ṣẹ́dà, ati aṣọ oniṣẹ-ọnà; iwọ jẹ iyẹfun daradara ati oyin, ati ororo: iwọ si ni ẹwà gidigidi, iwọ si gbilẹ di ijọba kan. 14 Okiki rẹ si kan lãrin awọn keferi nitori ẹwà rẹ: nitori iwọ pé nipa ẹwà mi, ti mo fi si ọ lara, ni Oluwa Ọlọrun wi. 15 Ṣugbọn iwọ gbẹkẹle ẹwà ara rẹ, o si huwa panṣaga nitori okìki rẹ, o si dà gbogbo agbere rẹ sori olukuluku ẹniti nkọja: tirẹ̀ ni. 16 Iwọ si mu ninu ẹwù rẹ, iwọ si fi aṣọ alaràbarà ṣe ibi giga rẹ lọṣọ, o si hùwa panṣaga nibẹ: iru nkan bẹ̃ kì yio de, bẹ̃ni kì yio ri bẹ̃. 17 Iwọ si mu ohun ọṣọ́ ẹlẹwà rẹ ninu wura mi, ati ninu fadaka mi, ti mo ti fun ọ, iwọ si ṣe àworán ọkunrin fun ara rẹ, o si fi wọn ṣe panṣaga, 18 Iwọ si mu ẹwù oniṣẹ-ọnà rẹ, o si fi bò wọn: iwọ si gbe ororo mi ati turari mi kalẹ niwaju wọn. 19 Onjẹ mi pẹlu ti mo ti fun ọ, iyẹfun daradara, ati ororo, ati oyin, ti mo fi bọ́ ọ, iwọ tilẹ gbe e kalẹ niwaju wọn fun õrùn didùn: bayi li o si ri, ni Oluwa Ọlọrun wi. 20 Pẹlupẹlu iwọ ti mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ti iwọ ti bi fun mi, awọn wọnyi ni iwọ si ti fi rubọ si wọn lati jẹ. Ohun kekere ha ni eyi ninu ìwa panṣaga rẹ, 21 Ti iwọ ti pa awọn ọmọ mi, ti o si fi wọn fun ni lati mu wọn kọja lãrin iná fun wọn? 22 Ati ni gbogbo ohun irira rẹ, ati panṣaga rẹ, iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, nigbati iwọ wà nihoho ti o si wà goloto, ti a si bà ọ jẹ ninu ẹjẹ rẹ. 23 O si ṣe lẹhin gbogbo ìwa buburu rẹ, (Egbe, egbe ni fun ọ! ni Oluwa Ọlọrun wi;) 24 Ti iwọ si kọ́ ile giga fun ara rẹ, ti iwọ si ṣe ibi giga ni gbogbo ita fun ara rẹ. 25 Iwọ ti kọ́ ibi giga rẹ ni gbogbo ikórita, o si ti sọ ẹwà rẹ di ikorira, o si ti ya ẹsẹ rẹ si gbogbo awọn ti nkọja, o si sọ panṣaga rẹ di pupọ. 26 Iwọ ti ba awọn ara Egipti aladugbo rẹ, ti o sanra ṣe agbere, o si ti sọ panṣaga rẹ di pupọ, lati mu mi binu. 27 Kiye si i, emi si ti nawọ mi le ọ lori, mo si ti bu onjẹ rẹ kù, mo si fi ọ fun ifẹ awọn ti o korira rẹ, awọn ọmọbinrin Filistia, ti ìwa ifẹkufẹ rẹ tì loju. 28 Iwọ ti ba awọn ara Assiria ṣe panṣaga pẹlu, nitori iwọ kò ni itẹlọrun; nitotọ, iwọ ti ba wọn ṣe panṣaga, sibẹsibẹ kò si le tẹ́ ọ lọrùn, 29 Iwọ si ti sọ agbere rẹ di pupọ lati ilẹ Kenaani de Kaldea; sibẹsibẹ eyi kò si tẹ́ ọ lọrun nihinyi. 30 Oluwa Ọlọrun wipe, aiyà rẹ ti ṣe alailera to, ti iwọ nṣe nkan wọnyi, iṣe agídi panṣaga obinrin; 31 Nitipe iwọ kọ́ ile giga rẹ ni gbogbo ikoríta, ti o si ṣe ibi giga rẹ ni gbogbo ita; iwọ kò si wa dabi panṣaga obinrin, nitipe iwọ gan ọ̀ya. 32 Ṣugbọn gẹgẹ bi aya ti o ṣe panṣaga, ti o gbà alejo dipo ọkọ rẹ̀! 33 Nwọn nfi ẹbùn fun gbogbo awọn panṣaga, ṣugbọn iwọ fi ẹbùn rẹ fun gbogbo awọn olufẹ rẹ, iwọ si ta wọn lọrẹ, ki nwọn le tọ̀ ọ wá ni ihà gbogbo fun panṣaga rẹ. 34 Eyiti o yatọ si ti awọn obinrin miran si mbẹ ninu rẹ, ninu panṣaga rẹ, ti ẹnikan kò tẹ̀le ọ lati ṣe panṣaga: ati nitipe iwọ ntọrẹ, ti a kò si tọrẹ fun ọ nitorina iwọ yatọ. 35 Nitorina, iwọ panṣaga, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: 36 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti a dà ẹgbin rẹ jade, ti a si ri ihoho rẹ nipa panṣaga rẹ pẹlu awọn olufẹ rẹ, ati pẹlu gbogbo oriṣa irira rẹ, ati nipa ẹjẹ awọn ọmọ rẹ, ti iwọ fi fun wọn: 37 Si kiye si i, Emi o kó gbogbo awọn olufẹ rẹ jọ, awọn ẹniti iwọ ti ba jaiye, ati gbogbo awọn ti iwọ ti fẹ, pẹlu gbogbo awọn ti iwọ ti korira; ani emi o gbá wọn jọ kakiri si ọ, emi o si fi ihoho rẹ hàn wọn, ki nwọn ki o le ri gbogbo ihoho rẹ. 38 Emi o si dá ọ lẹjọ, gẹgẹ bi a ti da awọn obinrin lẹjọ ti o ba igbeyawo jẹ ti nwọn si ta ẹjẹ silẹ; emi o si fi ẹjẹ fun ọ, ni irúnu ati ni ijowu. 39 Emi o si fi ọ le wọn lọwọ pẹlu, nwọn o si wo ibi giga rẹ, nwọn o si wo ibi giga rẹ palẹ: nwọn o si bọ aṣọ rẹ pẹlu, nwọn o si gbà ohun ọṣọ rẹ didara, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho, ati ni goloto. 40 Nwọn o mu ẹgbẹ́ kan wá si ọ pẹlu, nwọn o si sọ ọ li okuta, nwọn o si fi idà wọn gún ọ yọ. 41 Nwọn o si fi iná kun gbogbo ile rẹ; nwọn o si mu idajọ ṣẹ si ọ lara niwaju obinrin pupọ; emi o si jẹ ki o fi panṣaga rẹ mọ, iwọ pẹlu kì yio si funni ni ọ̀ya mọ. 42 Bẹ̃ni emi o jẹ ki irúnu mi si ọ ki o dá, owú mi yio si kuro lọdọ rẹ, emi o si dakẹjẹ, emi kì yio binu mọ. 43 Nitoripe iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, ṣugbọn o si mu mi kanra ninu gbogbo nkan wọnyi; si kiye si i, nitorina emi pẹlu o san ẹsan ọ̀na rẹ si ọ lori, ni Oluwa Ọlọrun wi: iwọ kì yio si ṣe ifẹkufẹ yi lori gbogbo ohun irira rẹ mọ. 44 Kiyesi i, olukuluku ẹniti npowe ni yio powe yi si ọ, wipe, Bi iyá ti ri, bẹ̃ni ọmọ rẹ̀ obinrin. 45 Iwọ ni ọmọ iyá rẹ ti o kọ̀ ọkọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀; iwọ ni arabinrin awọn arabinrin rẹ, ti o kọ̀ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn: ará Hiti ni iyá rẹ, ará Amori si ni baba rẹ. 46 Ẹgbọn rẹ obinrin si ni Samaria, on ati awọn ọmọbinrin rẹ ti ngbe ọwọ́ osì rẹ: ati aburo rẹ obinrin ti ngbe ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin. 47 Ṣugbọn iwọ kò rin ni ọ̀na wọn, iwọ kò si ṣe gẹgẹ bi irira wọn: ṣugbọn, bi ẹnipe ohun kekere ni eyini, iwọ bajẹ jù wọn lọ ni gbogbo ọ̀na rẹ. 48 Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, Sodomu arabinrin rẹ, on, tabi awọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò ṣe gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin. 49 Kiyesi i, ẹ̀ṣẹ Sodomu arabinrin rẹ niyi, irera, onjẹ ajẹyo, ati ọ̀pọlọpọ orayè wà ninu rẹ̀, ati ninu awọn ọmọ rẹ̀ obinrin; bẹ̃ni on kò mu ọwọ́ talaka ati alaini lokun. 50 Nwọn si gberaga, nwọn si ṣe ohun irira niwaju mi: nitorina ni mo mu wọn kuro gẹgẹ bi mo ti ri pe o dara. 51 Bẹ̃ni Samaria kò dá abọ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ: ṣugbọn iwọ sọ ohun irira rẹ di pupọ jù wọn lọ, o si ti da awọn arabinrin rẹ lare ninu gbogbo ohun irira rẹ ti iwọ ti ṣe. 52 Iwọ pẹlu, ti o ti da awọn arabinrin rẹ lẹbi, ru itiju ara rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ ti iwọ ti ṣe ni iṣe irira jù wọn lọ: awọn ṣe olododo jù iwọ lọ; nitotọ, ki iwọ ki o dãmu pẹlu, si ru itiju rẹ, nitipe iwọ dá awọn arabinrin rẹ lare. 53 Nigbati mo ba tun mu igbèkun wọn wá, igbèkun Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, pẹlu igbèkun Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nigbana li emi o tun mu igbèkun awọn onde rẹ wá lãrin wọn: 54 Ki iwọ ki o le ru itiju ara rẹ, ki o si le dãmu ni gbogbo eyi ti o ti ṣe, nitipe iwọ jẹ itunu fun wọn. 55 Nigbati awọn arabinrin rẹ Sodomu, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ba pada si ipò wọn iṣaju, ti Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin ba pada si ipò wọn iṣaju, nigbana ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin yio pada si ipò nyin iṣaju. 56 Nitori ẹnu rẹ kò da orukọ Sodomu arabinrin rẹ li ọjọ irera rẹ, 57 Ki a to ri ìwa buburu rẹ, bi akoko ti awọn ọmọbinrin Siria gàn ọ, ati gbogbo awọn ti o wà yi i ka, awọn ọmọbinrin Filistia ti o gàn ọ ka kiri. 58 Iwọ ti ru ifẹkufẹ rẹ ati ohun irira rẹ, ni Oluwa wi. 59 Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Emi o tilẹ ba ọ lò gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, ti iwọ ti gàn ibura nipa biba majẹmu jẹ. 60 Ṣugbọn emi o ranti majẹmu mi pẹlu rẹ, ni ọjọ ewe rẹ, emi o si gbe majẹmu aiyeraiye kalẹ fun ọ. 61 Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ. 62 Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ pẹlu rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 63 Ki iwọ ki o le ranti, ki o si le dãmu, ki iwọ ki o má si le yà ẹnu rẹ mọ nitori itiju rẹ, nigbati inu mi ba tutù si ọ, nitori ohun ti iwọ ti ṣe, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 17

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, pa alọ́ kan, si pa owe kan fun ile Israeli; 3 Si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Idì nla kan, pẹlu apá nla, alapá gigùn, o kún fun iyẹ́; ti o ni àwọ alaràbarà wá si Lebanoni, o si mu ẹka igi Kedari ti o ga julọ. 4 O ke ori ọ̀munú ẹka rẹ̀ kuro, o si mu u lọ si ilẹ òwo kan; o gbe e kalẹ ni ilu awọn oniṣòwo. 5 O mu ninu irugbìn ilẹ na pẹlu, o si gbìn i sinu oko daradara kan; o fi si ibi omi nla, o si gbe e kalẹ bi igi willo. 6 O si dagba, o si di igi àjara ti o bò ti o kuru, ẹka ẹniti o tẹ̀ sọdọ rẹ̀, gbòngbo rẹ̀ si wà labẹ rẹ̀; bẹ̃ni o di ajara, o si pa ẹka, o si yọ ọ̀munú jade. 7 Idì nla miran si wà pẹlu apá nla ati iyẹ́ pupọ: si kiye si i, àjara yi tẹ̀ gbòngbo rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si yọ ẹka rẹ̀ sọdọ rẹ̀, ki o le ma b'omi si i ninu aporo ọgbà rẹ̀. 8 Ilẹ rere lẹba omi nla ni a gbìn i si, ki o le bà yọ ẹka jade, ki o si le so eso, ki o le jẹ́ àjara rere. 9 Wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; yio ha gbà? on kì yio hú gbòngbo rẹ̀, kì yio si ka eso rẹ̀ kuro, ki o le rọ? yio rọ ninu gbogbo ewe rirú rẹ̀, ani laisi agbara nla tabi enia pupọ̀ lati fà a tu pẹlu gbòngbo rẹ̀. 10 Nitõtọ, kiye si i, bi a ti gbìn i yi, yio ha gbà? kì yio ha rẹ̀ patapata? nigbati afẹfẹ ilà-õrun ba kàn a? yio rẹ̀ ninu aporo ti o ti hù. 11 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 12 Sọ nisisiyi fun ọlọ̀tẹ ile na pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohun ti nkan wọnyi jasi? Sọ fun wọn, kiyesi i, ọba Babiloni de Jerusalemu, o si ti mu ọba ibẹ ati awọn ọmọ-alade ibẹ, o si mu wọn pẹlu rẹ̀ lọ si Babiloni: 13 O si ti mu ninu iru-ọmọ ọba, o si bá a dá majẹmu, o si ti mu u bura: o si mu awọn alagbara ilẹ na pẹlu: 14 Ki ijọba na le jẹ alailọla, ki o má le gbe ara rẹ̀ soke, ki o le duro nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ. 15 Ṣugbọn on ṣọ̀tẹ si i ni rirán awọn ikọ̀ rẹ̀ lọ si Egipti, ki nwọn ki o le fi ẹṣin fun u ati enia pupọ. Yio ha sàn a? ẹniti nṣe iru nkan wọnyi yio ha bọ́? tabi yio dalẹ tan ki o si bọ́? 16 Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nitotọ ibi ti ọba ngbe ti o fi i jọba, ibura ẹniti o gàn, majẹmu ẹniti o si bajẹ, ani lọdọ rẹ̀ lãrin Babiloni ni yio kú. 17 Bẹ̃ni Farao ti on ti ogun rẹ̀ ti o li agbara ati ẹgbẹ́ nla kì yio ṣe fun u ninu ogun, nipa mimọ odi, ati kikọle iṣọ́ ti o li agbara, lati ke enia pupọ̀ kuro: 18 Nitoriti o gàn ibura nipa didalẹ, kiye si i, o ti fi ọwọ́ rẹ̀ fun ni, o si ti ṣe gbogbo nkan wọnyi, kì yio bọ́. 19 Nitorina bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi mo ti wà, dajudaju ibura mi ti o ti gàn, ati majẹmu mi ti o ti dà, ani on li emi o san si ori on tikalarẹ̀. 20 Emi o si nà àwọn mi si i lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi; emi o si mu u de Babiloni, emi o si ba a rojọ nibẹ, nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti da si mi. 21 Ati gbogbo awọn isánsa rẹ̀ pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ́-ogun rẹ̀, ni yio ti oju idà ṣubu; awọn ti o si kù ni a o tuka si gbogbo ẹfũfu: ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti sọ ọ. 22 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ninu ẹka ti o ga jùlọ, ninu igi Kedari giga; emi o si lọ́ ọ, emi o ke ọ̀munú ẹka kan kuro ninu ọ̀munú ẹka rẹ̀; emi o si gbìn i sori oke giga kan ti o si hàn: 23 Lori oke giga ti Israeli ni emi o gbìn i si, yio si yọ ẹka; yio si so eso, yio si jẹ igi Kedari daradara; labẹ rẹ̀ ni gbogbo ẹiyẹ oniruru iyẹ́ o si gbe; ninu ojiji ẹka rẹ̀ ni nwọn o gbe. 24 Gbogbo igi inu igbẹ ni yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti mu igi giga walẹ, ti mo ti gbe igi rirẹlẹ soke, ti mo ti mu igi tutù gbẹ, ti mo si ti mu igi gbigbẹ ruwé: emi Oluwa li o ti sọ ti mo si ti ṣe e.

Esekieli 18

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Kini ẹnyin rò ti ẹnyin fi npowe yi niti ilẹ Israeli, pe, Awọn baba ti jẹ eso àjara kíkan, ehin awọn ọmọ si kan. 3 Oluwa Ọlọrun wipe, bi mo ti wà, ẹnyin kì yio ri àye lati powe yi mọ ni ilẹ Israeli. 4 Kiye si i, gbogbo ọkàn ni t'emi; gẹgẹ bi ọkàn baba ti jẹ t'emi, bẹ̃ni t'emi ni ọkàn ọmọ pẹlu; ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú. 5 Ṣugbọn bi enia kan ba ṣe olõtọ, ti o si ṣe eyiti o tọ ati eyiti o yẹ, 6 Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀. 7 Ti kò si ni ẹnikan lara, ṣugbọn ti o ti fi ohun ògo onigbèse fun u, ti kò fi agbara kó ẹnikẹni, ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹwu bo ẹni-ihoho. 8 Ẹniti kò fi fun ni lati gba ẹdá, bẹ̃ni kò gba elékele, ti o ti fa ọwọ́ rẹ̀ kuro ninu aiṣedẽde, ti o ti mu idajọ otitọ ṣẹ lãrin ọkunrin ati ọkunrin, 9 Ti o ti rìn ninu aṣẹ mi, ti o si ti pa idajọ mi mọ, lati hùwa titọ́; on ṣe olõtọ, yiyè ni yio yè, ni Oluwa Ọlọrun wi. 10 Bi o ba bi ọmọkunrin kan ti iṣe ọlọṣà, oluta ẹ̀jẹ silẹ, ti o si nṣe ohun ti o jọ ọkan ninu nkan wọnyi si arakunrin rẹ̀. 11 Ti kò si ṣe ọkan ninu gbogbo iṣẹ wọnni, ṣugbọn ti o tilẹ ti jẹun lori oke, ti o si ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, 12 Ti o ti ni talaka ati alaini lara; ti o ti fi agbara koni, ti kò mu ohun ògo pada, ti o ti gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa, ti o ti ṣe ohun irira, 13 Ti o ti fi fun ni lati gba ẹdá, ti o si ti gba èle: on o ha yè bẹ̃? on ki yio yè: on ti ṣe gbogbo ohun irira wọnyi; kikú ni yio kú: ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. 14 Si kiye si i, bi o ba bi ọmọkunrin ti o ri gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si bẹ̀ru, ti kò si ṣe iru rẹ̀, 15 Ti kò si jẹun lori oke, ti kò gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa ile Israeli, ti kò ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, 16 Ti kò ni ẹnikan lara, ti kò dá ohun ògo duro, ti kò fi agbara koni, ṣugbọn ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹ̀wu bo ẹni-ihoho, 17 Ti o ti mu ọwọ́ rẹ̀ kuro lara ẹni-inilara, ti kò ti gba ẹdá tabi elé ti o ti mu idajọ mi ṣẹ, ti o ti rìn ninu aṣẹ mi; on kì yio kú nitori aiṣedẽde baba rẹ̀, yiyè ni yio yè. 18 Bi o ṣe ti baba rẹ̀, nitoripe o fi ikà ninilara, ti o fi agbara ko arakunrin rẹ̀; ti o ṣe eyiti kò dara lãrin enia rẹ̀, kiye si i, on o tilẹ kú ninu aiṣedẽde rẹ̀. 19 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẽṣe? ọmọ kò ha ru aiṣedẽde baba? Nigbati ọmọ ti ṣe eyiti o tọ́ ati eyiti o yẹ, ti o si ti pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ti ṣe wọn, yiyè ni yio yè. 20 Ọkàn ti o ba ṣẹ̀, on o kú. Ọmọ kì yio rù aiṣedẽde baba, bẹ̃ni baba kì yio rù aiṣedẽde ọmọ: ododo olododo yio wà lori rẹ̀, ìwa buburu enia buburu yio si wà lori rẹ̀. 21 Ṣugbọn bi enia buburu yio ba yipada kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ti o si pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ṣe eyi ti o tọ́, ati eyiti o yẹ, yiyè ni yio yè, on kì yio kú. 22 Gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, a kì yio ranti wọn si i: ninu ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni on o yè. 23 Emi ha ni inu-didùn rara pe ki enia buburu ki o kú? ni Oluwa Ọlọrun wi: kò ṣepe ki o yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, ki o si yè? 24 Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yè? gbogbo ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni a kì yio ranti: ninu irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ninu wọn ni yio kú. 25 Ṣugbọn ẹnyin wipe, ọ̀na Oluwa kò gún. Gbọ́ nisisiyi, iwọ ile Israeli; ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún? 26 Nigbati olododo kan ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedẽde, ti o si kú ninu wọn; nitori aiṣedẽde rẹ̀ ti o ti ṣe ni yio kú. 27 Ẹwẹ, nigbati enia buburu ba yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si ṣe eyiti o tọ́, ati eyiti o yẹ, on o gba ọkàn rẹ̀ là lãye. 28 Nitoripe o bẹ̀ru o si yipada kuro ninu gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, yiyè ni yio yè, on kì yio kú. 29 Ṣugbọn ile Israeli wipe, Ọ̀na Oluwa kò gún. Ile Israeli, ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún? 30 Nitorina emi o dá nyin lẹjọ, ile Israeli, olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ẹ yipada, ki ẹ si yi kuro ninu gbogbo irekọja nyin; bẹ̃ni aiṣedẽde kì yio jẹ iparun nyin. 31 Ẹ ta gbogbo irekọja nyin nù kuro lọdọ nyin, nipa eyiti ẹnyin fi rekọja; ẹ si dá ọkàn titun ati ẹmi titun fun ara nyin: nitori kini ẹnyin o ṣe kú, ile Israeli? 32 Nitoripe emi kò ni inu didùn si ikú ẹniti o kú, ni Oluwa Ọlọrun wi: nitorina ẹ yi ara nyin pada, ki ẹ si yè.

Esekieli 19

1 PẸLUPẸLU iwọ pohùn-rére ẹkun fun awọn ọmọ-alade Israeli, 2 Si wipe, Kini iyá rẹ? Abo kiniun: o dubulẹ lãrin kiniun, o bọ́ awọn ọmọ rẹ lãrin ọmọ kiniun. 3 O si tọ́ ọkan ninu ọmọ rẹ̀ dàgba: o di ọmọ kiniun, o si kọ́ ati ṣọdẹ; o pa enia jẹ. 4 Awọn orilẹ-ède pẹlu gburo rẹ̀: a mu u ninu iho wọn, nwọn si fi ẹ̀wọn mu u lọ si ilẹ Egipti. 5 Nigbati o si ri pe on si duro, ti ireti rẹ̀ si sọnu, nigbana ni o mu omiran ninu ọmọ rẹ̀, o si sọ ọ di ọmọ kiniun. 6 On si lọ soke lọ sodo lãrin awọn kiniun, o di ọmọ kiniun, o si kọ́ lati ṣọdẹ, o si pa enia jẹ. 7 On si mọ̀ awọn opo wọn, o si sọ ilu-nla wọn di ahoro; ilẹ na di ahoro, ati ẹkún rẹ̀, pẹlu nipa ariwo kike ramuramu rẹ̀. 8 Nigbana ni awọn orilẹ-ède kó tì i nihà gbogbo lati ìgberiko wá, nwọn si na awọ̀n wọn le e lori: a mu u ninu iho wọn. 9 Nwọn si fi i sinu ẹṣọ́ ninu ẹ̀wọn, nwọn si mu u wá sọdọ ọba Babiloni: nwọn mu u lọ sinu ilu olodi, ki a má ba gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ lori oke Israeli. 10 Iyá rẹ dabi àjara kan ninu ẹjẹ rẹ, ti a gbìn si eti odò, on kún fun eso, o si kún fun ẹka nitori ọ̀pọlọpọ odò. 11 O si ni ọpá ti o le fun ọpá-ade awọn ti o jẹ oye; giga rẹ̀ li a gbega lãrin ẹka gigun, o si farahàn ninu giga rẹ̀ pẹlu ọ̀pọlọpọ ẹka rẹ̀. 12 Ṣugbọn a fã a tu ni irúnu, a wọ ọ lulẹ, ẹfũfu ila-õrun si gbe eso rẹ̀, ọpá lile rẹ̀ ti ṣẹ, o si rọ; iná jo o run. 13 Nisisiyi a si gbìn i si aginju, ni ilẹ gbigbẹ ati ilẹ ongbẹ. 14 Iná si jade lati inu ọpá kan ninu ẹka rẹ̀, ti o ti jo eso rẹ̀ run, tobẹ̃ ti kò fi ni ẹka ti o le lati ṣe ọpa lati joye. Eyi ni ohùnrére ẹkun, yio si jẹ ohùn-rére ẹkun.

Esekieli 20

1 O si ṣe ni ọdun keje ni oṣu karun, ni ọjọ kẹwa oṣu, ti awọn kan ninu awọn àgba Israeli wá ibere lọwọ Oluwa, nwọn si joko niwaju mi. 2 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 3 Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere. 4 Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn. 5 Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: 6 Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ. 7 Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin. 8 Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti. 9 Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi; ki o má bà bajẹ niwaju awọn keferi, lãrin ẹniti nwọn wà, loju ẹniti mo sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn, ni mimu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti. 10 Mo si jẹ ki wọn lọ kuro ni ilẹ Egipti, mo si mu wọn wá si aginju. 11 Mo si fi aṣẹ mi fun wọn, mo si fi idajọ mi hàn wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn. 12 Pẹlupẹlu mo si fun wọn ni ọjọ isimi mi, lati ṣe àmi lãrin t'emi ti wọn, ki nwọn ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa ti o yà wọn si mimọ́. 13 Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run. 14 Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má ba di ibajẹ niwaju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade. 15 Pẹlupẹlu mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn ni aginju pe emi kò ni mu wọn de ilẹ ti mo ti fi fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ; 16 Nitoriti nwọn gàn idajọ mi, nwọn kò si rìn ninu aṣẹ mi, ṣugbọn nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: nitoripe ọkàn wọn tẹ̀le oriṣa wọn. 17 Ṣugbọn oju mi dá wọn si ki emi má ba pa wọn, bẹ̃ni emi kò ṣe wọn li aṣetan ni aginju. 18 Ṣugbọn mo sọ fun awọn ọmọ wọn li aginju pe, Ẹ máṣe rìn ninu aṣẹ baba nyin, ẹ má si ṣe kiyesi idajọ wọn, ẹ má si fi oriṣa wọn sọ ara nyin di aimọ́: 19 Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: ẹ rìn ninu aṣẹ mi, ẹ si pa idajọ mi mọ, ẹ si ṣe wọn; 20 Ẹ si bọ̀wọ fun ọjọ isimi mi; nwọn o si jẹ àmi lãrin t'emi ti nyin, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa Ọlọrun nyin. 21 Ṣugbọn awọn ọmọ na ṣọ̀tẹ si mi: nwọn kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni nwọn kò pa idajọ mi mọ lati ṣe wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn; nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: mo si wipe, Emi o da irúnu mi sori wọn, lati pari ibinu mi sori wọn li aginju. 22 Ṣugbọn mo fà ọwọ́ mi sẹhìn, mo si ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má bà di ibajẹ li oju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade. 23 Mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn pẹlu li aginju, lati tú wọn ka lãrin awọn keferi, ati lati fọ́n wọn ká ilẹ gbogbo; 24 Nitoripe nwọn kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn nwọn kẹgàn aṣẹ mi, nwọn si ti bà ọjọ isimi mi jẹ, oju wọn si wà lara oriṣa baba wọn. 25 Nitorina mo fun wọn ni aṣẹ pẹlu ti kò dara, ati idajọ nipa eyiti wọn kì yio fi le yè; 26 Emi si bà wọn jẹ́ ninu ẹ̀bun ara wọn, nitipe nwọn mu gbogbo awọn akọbi kọja lãrin iná, ki emi ba le sọ wọn di ahoro, ki nwọn le bà mọ̀ pe emi ni Oluwa. 27 Nitorina, ọmọ enia, sọ fun ile Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ninu eyi pẹlu baba nyin ti sọ̀rọ odi si mi, nitipe nwọn ti dẹṣẹ si mi. 28 Nitori nigbati mo ti mu wọn de ilẹ, niti eyiti mo gbé ọwọ́ mi soke lati fi i fun wọn, nigbana ni nwọn ri olukuluku oke giga, ati gbogbo igi bibò, nwọn si ru ẹbọ wọn nibẹ, nwọn si gbe imunibinu ọrẹ wọn kalẹ nibẹ: nibẹ pẹlu ni nwọn ṣe õrun didùn wọn, nwọn si ta ohun-ọrẹ mimu silẹ nibẹ. 29 Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Kini ibi giga ti ẹnyin nlọ na? Orukọ rẹ̀ ni a si npe ni Bama titi o fi di oni oloni. 30 Si wi fun ile Israeli pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; A bà nyin jẹ́ gẹgẹ bi baba nyin? ẹnyin si ṣe agbère gẹgẹ bi ohun-irira wọn? 31 Nitori nigbati ẹnyin nta ọrẹ nyin, nigbati ẹnyin mu ọmọ nyin kọja lãrin iná, ẹnyin fi oriṣa nyin bà ara nyin jẹ́, ani titi o fi di oni oloni: ẹnyin o ha si bere lọwọ mi, Iwọ ile Israeli? Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere. 32 Eyiti o si wá si iye nyin kì yio wà rara; ti ẹnyin wipe, Awa o wà bi awọn keferi, gẹgẹ bi idile awọn orilẹ-ède lati bọ igi ati okuta. 33 Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ nipa agbara ọwọ́, ati ninà apa, pẹlu irúnu ti a dà jade li emi o fi jọba lori nyin: 34 Emi o si mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, emi o si ṣà nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ka si, pẹlu ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ati pẹlu irúnu ti a dà jade. 35 Emi o si mu nyin wá si aginju awọn enia, nibẹ ni emi o si bá nyin rojọ lojukoju. 36 Gẹgẹ bi mo ti dá awọn baba nyin lẹjọ li aginju ilẹ Egipti, bẹ̃ni emi o bá nyin rojọ, ni Oluwa Ọlọrun wi. 37 Emi o si mu nyin kọja labẹ ọpá, emi o si mu nyin wá si ìde majẹmu: 38 Emi o si ṣà awọn ọlọ̀tẹ kuro lãrin nyin, ati awọn olurekọja, emi o mu wọn jade kuro ni ilẹ ti wọn gbe ṣe atipo, nwọn kì yio si wọ ilẹ Israeli: ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa. 39 Bi o ṣe ti nyin, ile Israeli, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi, Ẹ lọ, olukuluku sìn oriṣa rẹ̀, ati lẹhin eyi pẹlu, bi ẹnyin kì yio ba fi eti si mi: ṣugbọn ẹ máṣe fi ẹ̀bun nyin ati oriṣa nyin bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ mọ. 40 Nitori lori oke mimọ́ mi, lori oke giga Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, nibẹ ni gbogbo ile Israeli, gbogbo wọn ni ilẹ na, yio sìn mi: nibẹ ni emi o gbà wọn, nibẹ ni emi o si bere ẹbọ nyin, ati ọrẹ akọso nyin, pẹlu ohun mimọ́ nyin. 41 Emi o gbà nyin pẹlu õrùn didùn nyin, nigbati mo mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, ti mo si ko nyin jọ lati ilẹ gbogbo nibiti a gbe ti tú nyin ká si; a o si yà mi si mimọ́ ninu nyin niwaju awọn keferi. 42 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi o mu nyin de ilẹ Israeli, si ilẹ niti eyiti o gbe ọwọ́ mi soke lati fi fun awọn baba nyin. 43 Nibẹ li ẹnyin o ranti ọ̀na nyin, ati gbogbo iṣe nyin, ninu eyiti a ti bà nyin jẹ; ẹ o si sú ara nyin loju ara nyin nitori gbogbo buburu ti ẹnyin ti ṣe. 44 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi ti ṣiṣẹ pẹlu nyin nitori orukọ mi, ki iṣe gẹgẹ bi ọ̀na buburu nyin, tabi gẹgẹ bi iṣe bibajẹ nyin, ẹnyin ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi. 45 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 46 Ọmọ enia, kọju rẹ siha gusù, si sọ ọ̀rọ rẹ siha gusù, si sọtẹlẹ si igbó oko gusù; 47 Si wi fun igbó gusù pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o da iná kan ninu rẹ, yio si jo olukuluku igi tutù ninu rẹ, ati olukuluku igi gbigbẹ: jijo ọwọ́ iná na ni a kì yio pa, ati gbogbo oju lati gusu de ariwa ni a o sun ninu rẹ̀. 48 Gbogbo ẹran-ara ni yio si ri i pe emi Oluwa li o ti da a, a kì yio pa a. 49 Nigbana ni mo wipe, A! Oluwa Ọlọrun, nwọn wi niti emi pe, Owe ki o npa yi?

Esekieli 21

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe. 2 Ọmọ enia, kọju rẹ sihà Jerusalemu, si sọ ọ̀rọ si ibi mimọ́ wọnni, si sọtẹlẹ si ilẹ Israeli. 3 Si wi fun ilẹ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ ọ, emi o si fa idà mi yọ kuro li akọ̀ rẹ̀, emi o si ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ. 4 Njẹ bi o ti ṣe pe emi o ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ, nitorina ni idà mi o ṣe jade lọ lati inu àkọ rẹ̀, si gbogbo ẹran-ara, lati gusù de ariwa: 5 Ki gbogbo ẹran-ara le mọ̀ pe emi Oluwa ti fà idà mi yọ kuro li àkọ rẹ̀: kì yio pada mọ lai. 6 Nitorina kerora, iwọ ọmọ enia, pẹlu ṣiṣẹ́ ẹgbẹ́ rẹ, ati pẹlu ikerora kikoro niwaju wọn. 7 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkerora? iwọ o dahùn wipe, Nitori ihìn na; nitoripe o de: olukuluku ọkàn ni yio yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yio si ṣe ailokun, olukuluku ẹmi yio si dakú, gbogbo ẽkún ni yio ṣe ailagbara bi omi: kiyesi i, o de, a o si mu u ṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi. 8 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, 9 Ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi li Oluwa wi; Wipe, Idà, idà ti a pọ́n, ti a si dán pẹlu: 10 A pọ́n ọ lati pa enia pupọ; a dán a lati ma kọ màna: awa o ha ma ṣe ariyá? ọgọ ọmọ mi, o gàn gbogbo igi. 11 On si ti fi i le ni lọwọ lati dán, ki a ba le lò o; idà yi li a pọ́n, ti a si dán, lati fi i le ọwọ́ apani. 12 Kigbe, ki o si wu, ọmọ enia: nitori yio wá sori awọn enia mi, yio wá sori gbogbo ọmọ-alade Israeli: ìbẹru nla yio wá sori awọn enia mi nitori idà na: nitorina lu itan rẹ. 13 Nitoripe idanwo ni, ki si ni bi idà na gàn ọgọ na? kì yio si mọ́, ni Oluwa Ọlọrun wi. 14 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ, si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, si jẹ ki idà ki o ṣẹ́po nigba kẹta, idà awọn ti a pa: idà awọn enia nla ti a pa ni, ti o wọ inu yara ikọ̀kọ wọn lọ. 15 Mo ti nà ṣonṣo idà si gbogbo bode wọn: ki aiya wọn le dakú, ati ki ahoro wọn le di pupọ: ã! a ti ṣe e dán, a ti pọ́n ọ mú silẹ fun pipa. 16 Iwọ gba ọ̀na kan tabi ọ̀na keji lọ, si apa ọtún tabi si òsi, nibikibi ti iwọ dojukọ. 17 Emi o si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, emi o si jẹ ki irúnu mi ki o simi: emi Oluwa li o ti wi bẹ̃. 18 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 19 Iwọ pẹlu, ọmọ enia, yan ọ̀na meji fun ara rẹ, ki idà ọba Babiloni ki o le wá: awọn mejeji yio jade lati ilẹ kanna wá: si yan ibi kan, yàn a ni ikorita ti o lọ si ilu-nla. 20 Yàn ọ̀na kan, ki idà na le wá si Rabba ti awọn ara Ammoni, ati si Juda ni Jerusalemu ti o li odi. 21 Nitori ọba Babiloni duro ni iyàna, lori ọ̀na meji, lati ma lo afọṣẹ: o mì ọfà rẹ̀, o da òriṣa, o wo ẹ̀dọ. 22 Li ọwọ́ ọtún rẹ̀ ni afọṣẹ Jerusalemu wà, lati yan õlù, lati ya ẹnu rẹ̀ ni pipa, lati gbohùn soke pẹlu ariwo, lati yan õlù si bode, lati mọ odi, ati lati kọ ile iṣọ́. 23 Afọ̀ṣẹ na yio si dabi eké fun wọn, loju awọn ti o ti bura fun wọn: ṣugbọn on o mu aiṣedẽde wá si iranti, ki a ba le mu wọn. 24 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe ẹnyin jẹ ki a ranti aiṣedẽde nyin, niti pe a ri irekọja nyin, tobẹ̃ ti ẹ̀ṣẹ nyin hàn, ni gbogbo iṣe nyin: nitoripe ẹnyin wá si iranti, ọwọ́ li a o fi mu nyin. 25 Ati iwọ, alailọ̀wọ ẹni-buburu ọmọ-alade Israeli, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedẽde ikẹhìn. 26 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Mu fila ọba kuro, si ṣi ade kuro; eyi kò ni jẹ ọkanna: gbe ẹniti o rẹlẹ ga, si rẹ̀ ẹniti o ga silẹ. 27 Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì i subu, kì yio si si mọ, titi igbati ẹniti o ni i ba de; emi o si fi fun u. 28 Ati iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti awọn ara Ammoni, ati niti ẹgàn wọn; ani ki iwọ wipe, Idà na, idà na ti a fà yọ, a ti dán a fun pipa, lati parun lati kọ màna. 29 Nigbati nwọn ri ohun asan si ọ, nigbati nwọn fọ̀ àfọṣẹ eke si ọ, lati mu ọ wá si ọrùn awọn ti a pa, ti ẹni-buburu, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigbati aiṣedẽde pin. 30 Tun mu ki o pada sinu àkọ rẹ̀! Emi o ṣe idajọ rẹ nibi ti a gbe ṣe ẹdá rẹ, ni ilẹ ibi rẹ. 31 Emi o dà ibinujẹ mi le ọ lori, ninu iná irúnu mi li emi o fẹ si ọ, emi o si fi ọ le awọn eniakenia lọwọ, ti nwọn ni ọgbọn lati parun. 32 Iwọ o jẹ́ igi fun iná; ẹjẹ rẹ yio wà lãrin ilẹ na; a kì yio ranti rẹ mọ: nitori emi Oluwa li o ti wi i.

Esekieli 22

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Njẹ, iwọ ọmọ enia, iwọ o ha ṣe idajọ, iwọ o ha ṣe idajọ ilu ẹlẹjẹ na? nitõtọ, iwọ o jẹ ki o mọ̀ ohun irira rẹ̀ gbogbo. 3 Nitorina, iwọ wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ilu ti o ta ẹjẹ silẹ lãrin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki o le de, o si ṣe oriṣa si ara rẹ̀ lati sọ ara rẹ̀ di aimọ́. 4 Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ. 5 Awọn ti o sunmọ tosí, ati awọn ti o jìna si ọ, yio fi ọ ṣẹ̀sin, iwọ ti a bà orukọ rẹ̀ jẹ, ti a si bà ninu jẹ pupọ. 6 Kiyesi i, awọn ọmọ-alade Israeli, olukuluku ninu agbara rẹ̀ wà ninu rẹ lati ta ẹjẹ silẹ. 7 Ninu rẹ ni nwọn kò ka baba ati iyá si: lãrin rẹ ni nwọn ti ni awọn alejo lara: ninu rẹ ni nwọn ti bà alaini-baba ati opo ninu jẹ. 8 Iwọ ti gan awọn ohun mimọ́ mi, o si ti sọ ọjọ isimi mi di ailọ̀wọ. 9 Ninu rẹ ni awọn ọkunrin ti o nṣe ofófo lati ta ẹjẹ silẹ wà: ninu rẹ ni nwọn si jẹun lori awọn oke: lãrin rẹ ni nwọn huwà ifẹkufẹ. 10 Ninu rẹ ni nwọn ti tu ihòho baba wọn: ninu rẹ ni nwọn ti tẹ́ obinrin ti a yà sapakan nitori aimọ́ rẹ̀ logo. 11 Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀. 12 Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi. 13 Kiyesi i, nitorina, mo ti fi ọwọ́ lu ọwọ̀ pọ̀ si ère aiṣõtọ rẹ ti o ti jẹ, ati si ẹjẹ rẹ ti o ti wà lãrin rẹ. 14 Ọkàn rẹ le gbà a, tabi ọwọ́ rẹ lè le, li ọjọ ti emi o ba ọ ṣe? emi Oluwa li o ti sọ ọ, emi o sì ṣe e. 15 Emi o fọ́n ọ ká sãrin awọn keferi, emi o si tú ọ ká si orilẹ-ède gbogbo, emi o si run ẽri rẹ kuro lara rẹ. 16 A o si sọ ọ di aìlọwọ ninu ara rẹ loju awọn keferi, iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 17 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 18 Ọmọ enia, ile Israeli di idarọ si mi: gbogbo wọn jẹ idẹ, ati tánganran, ati irin, ati ojé, lãrin ileru; ani nwọn jẹ idarọ fadaka. 19 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti gbogbo nyin di idarọ, kiyesi i, nitorina emi o ko nyin jọ si ãrin Jerusalemu. 20 Gẹgẹ bi nwọn ti ima ko fadaka, ati idẹ, ati irin, ati ojé, ati tánganran jọ si ãrin ileru, lati fin iná si i, ki a lè yọ́ ọ, bẹ̃ni emi o kó nyin ni ibinu mi, ati irúnu mi, emi o si fi nyin sibẹ emi o yọ́ nyin. 21 Nitotọ, emi o ko nyin jọ, emi o si fin iná ibinu mi si nyin lara, ẹ o si di yiyọ́ lãrin rẹ̀. 22 Bi a ti iyọ́ fadaka lãrin ileru, bẹ̃li a o yọ́ nyin lãrin rẹ̀; ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti dà irúnu mi si nyin lori. 23 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 24 Ọmọ enia, sọ fun u, Iwọ ni ilẹ ti a kò gbá mọ́, ti a kò si rọ̀jo si i lori lọjọ ibinu. 25 Ìditẹ awọn wolĩ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, bi kiniun ti nke ramuramu ti nṣọdẹ; nwọn ti jẹ ọkàn run, nwọn ti kó ohun iṣura ati ohun iyebiye; nwọn ti sọ ọ̀pọlọpọ di opó fun u lãrin rẹ̀. 26 Awọn alufa rẹ̀ ti rú ofin mi, nwọn si fi sọ ohun mimọ́ mi di àilọwọ: nwọn kò fi ìyatọ sãrin ohun mimọ́ ati àilọwọ, bẹ̃ni nwọn kò fi ìyatọ hàn lãrin ohun aimọ́, ati mimọ́, nwọn si ti fi oju wọn pamọ kuro li ọjọ isimi mi, mo si di ẹmi àilọwọ lãrin wọn. 27 Awọn ọmọ-alade ãrin rẹ̀ dabi kõkò ti nṣọdẹ, lati tàjẹ silẹ, lati pa ọkàn run, lati jère aiṣõtọ. 28 Ati awọn wolĩ rẹ̀ ti fi ẹfun kùn wọn, nwọn nri asan, nwọn si nfọ afọ̀ṣẹ eke si wọn, wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, nigbati o ṣepe Oluwa kò sọ̀rọ. 29 Awọn enia ilẹ na, ti lo ìwa-ininilara, nwọn si ja olè, nwọn si ti bi awọn talaka ati alaini ninu: nitõtọ, nwọn ti ni alejò lara lainidi. 30 Emi si wá ẹnikan lãrin wọn, ti ibá tun odi na mọ, ti ibá duro ni ibiti o ya na niwaju mi fun ilẹ na, ki emi má bà parun: ṣugbọn emi kò ri ẹnikan. 31 Nitorina ni mo ṣe dà ibinu mi si wọn lori; mo ti fi iná ibinu mi run wọn: mo si ti fi ọ̀na wọn gbẹsan lori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 23

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, obinrin meji wà, ọmọbinrin iyá kanna: 3 Nwọn si ṣe panṣaga ni Egipti; nwọn ṣe panṣaga nigba ewe wọn: nibẹ ni a tẹ̀ ọmú wọn, nibẹ ni wọn si rin ọmú igbà wundia wọn. 4 Orukọ wọn si ni Ahola, ti iṣe ẹ̀gbọn, ati Aholiba aburo rẹ̀: ti emi si ni nwọn, nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Orukọ wọn ni eyi; Samaria ni Ahola, Jerusalemu si li Aholiba. 5 Ahola si ṣe panṣaga, nigbati o jẹ ti emi; o si fẹ awọn olufẹ rẹ̀ li afẹju, awọn ara Assiria aladugbo rẹ̀, 6 Ti a fi aṣọ alaro bò lara, awọn balogun ati awọn olori, gbogbo nwọn jẹ ọmọkunrin ti o wun ni, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin. 7 Bayi li o ṣe panṣaga rẹ̀ pẹlu wọn, pẹlu gbogbo awọn aṣàyan ọkunrin Assiria, ati pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ li afẹjù: o fi gbogbo oriṣa wọn ba ara rẹ̀ jẹ. 8 Bẹ̃ni kò fi panṣaga rẹ̀ ti o mu ti Egipti wá silẹ: nitori nigba ewe rẹ̀ ni nwọn ba a sùn, nwọn si rin ọmú ìgba wundia rẹ̀, nwọn si dà panṣaga wọn si i lara. 9 Nitorina ni mo ti fi le ọwọ́ awọn olufẹ rẹ̀, le ọwọ́ awọn ara Assiria, awọn ti o fẹ li afẹju. 10 Awọn wọnyi tu ìhoho rẹ̀ silẹ: nwọn mu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nwọn si fi idà pa a: o si di ẹni-olokiki lãrin awọn obinrin; nitori pe nwọn ti mu idajọ ṣẹ si i lara. 11 Nigbati Aholiba aburo ri eyi, o wà bàjẹ ju on lọ ni ìwa ifẹkufẹ rẹ̀, ati ni panṣaga rẹ̀ ju ẹ̀gbọn rẹ̀ lọ ni panṣaga rẹ̀. 12 O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni. 13 Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan. 14 Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan, 15 Ti a dì li àmure li ẹ̀gbẹ, ti nwọn ṣe aṣejù ni rirẹ lawani ori wọn, gbogbo wọn jẹ ajagun-kẹkẹ́ ti a ba ma wò, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Babiloni ti Kaldea, ilẹ ibi wọn: 16 Bi o si ti fi oju rẹ̀ ri wọn, o fẹ wọn li afẹjù, o si ran onṣẹ si wọn si Kaldea. 17 Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn. 18 Bayi li o tú idi panṣaga rẹ̀ silẹ, o si tú ihòho rẹ̀ silẹ: nigbana li ọkàn mi ṣi kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn mi ti ṣi kuro lọdọ ẹ̀gbọn rẹ̀. 19 Sibẹsibẹ o mu panṣaga rẹ̀ bi si i ni pipè ọjọ ewe rẹ̀ si iranti, ninu eyi ti o ti ṣe panṣaga ni ilẹ Egipti. 20 Nitoripe o fẹ awọn olufẹ wọn li afẹju, ẹran-ara awọn ti o dabi ẹran-ara kẹtẹkẹtẹ, ati irú awọn ẹni ti o dabi irú ẹṣin. 21 Bayi ni iwọ pe ìwa ifẹkufẹ ìgba ewe rẹ wá si iranti, niti ririn ori ọmú rẹ lati ọwọ́ awọn ara Egipti, fun ọmú ìgba ewe rẹ. 22 Nitorina, iwọ Aholiba, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi o gbe awọn olufẹ rẹ dide si ọ, lọdọ awọn ti ọkàn rẹ ti ṣi, emi o si mu wọn doju kọ ọ niha gbogbo. 23 Awọn ara Babiloni, ati gbogbo awọn ara Kaldea, Pekodu, ati Ṣoa, ati Koa, ati gbogbo awọn ara Assiria pẹlu wọn: gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wunni, balogun ati awọn olori, awọn ọkunrin ti o li okiki, gbogbo wọn li o ngun ẹṣin. 24 Nwọn o si wá fi kẹkẹ́ ogun, kẹkẹ́ ẹrù, ati kekẹ́ kekeke doju kọ ọ, ati pẹlu ìgbajọ ọ̀pọ enia, awọn ti yio doju asà, ati apata, ati akoro kọ ọ niha gbogbo: emi o si gbe idajọ kalẹ niwaju wọn, nwọn o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi idajọ wọn. 25 Emi o si doju owu mi kọ ọ, nwọn o si fi irúnu ba ọ lò: nwọn o fá imu rẹ ati eti rẹ; ati awọn ti o kù ninu rẹ yio ti ọwọ́ idà ṣubu: nwọn o mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin lọ, ati awọn ti o kù ninu rẹ, li a o fi iná run. 26 Nwọn o si bọ aṣọ rẹ, nwọn o si mu ohun ọṣọ daradara rẹ lọ. 27 Bayi li emi o jẹ ki ifẹkufẹ rẹ mọ kuro lọdọ rẹ, ati panṣaga rẹ ti o mu ti ilẹ Egipti wá; tobẹ̃, ti iwọ kì yio gboju rẹ soke si wọn, bẹ̃ni iwọ kì yio si ranti Egipti mọ. 28 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ọ le awọn ti iwọ korira lọwọ, li ọwọ́ awọn ẹniti ọkàn rẹ ṣi: 29 Nwọn o si ba ọ lo ilo irira, nwọn o si ko gbogbo iṣẹ rẹ lọ, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho ati ni goloto: ati ihoho panṣaga rẹ li a o tu silẹ, ti ifẹkufẹ rẹ, ati panṣaga rẹ. 30 Emi o ṣe gbogbo nkan wọnyi si ọ, nitori pe iwọ ti bá awọn keferi ṣe agbere lọ, ati pe iwọ ti fi oriṣa wọn bà ara rẹ jẹ́. 31 Iwọ ti rìn li ọ̀na ẹ̀gbọn rẹ, nitorina li emi o fi ago rẹ̀ le ọ lọwọ. 32 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ o mu ninu ago ẹ̀gbọn rẹ ti o jin, ti o si tobi: a o fi ọ rẹrin ẹlẹya, a o yọ ṣuti si ọ; o gbà pupọ. 33 A o fi ọti pa ọ, a o si fi ikãnu kún ọ, pẹlu ago iyanu ati idahoro, pẹlu ago Samaria ẹ̀gbọn rẹ. 34 Iwọ o tilẹ mu u, iwọ o si fi ẹnu fa ọti jade, iwọ o si fọ apãdi na, iwọ o si fà ọmú ara rẹ tu, nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi. 35 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe iwọ ti gbagbe mi ti o si ti sọ mi si ẹhìn rẹ, nitorina iwọ rù ifẹkufẹ rẹ pẹlu ati panṣaga rẹ, 36 Oluwa tun sọ fun mi pe; Ọmọ enia, iwọ o ha dá Ahola ati Aholiba lẹ́jọ? nitõtọ sọ irira wọn fun wọn; 37 Pe, nwọn ti ṣe panṣaga ẹ̀jẹ si mbẹ lọwọ wọn, ati nipasẹ oriṣa wọn ni nwọn ti ṣe panṣaga, nwọn si ti jẹ ki awọn ọmọ wọn, ti nwọn bi fun mi, kọja lãrin iná fun wọn, lati run wọn. 38 Eyi ni nwọn si ṣe si mi; nwọn ti bà ibi mimọ́ mi jẹ li ọjọ kanna, nwọn sọ ọjọ isimi mi di aìlọwọ. 39 Nitoripe igbati nwọn pa awọn ọmọ wọn fun oriṣa wọn, nigbana ni nwọn wá ni ijọ kanna si ibi mimọ́ mi, lati sọ ọ di àilọwọ; si kiye si i, bayi ni nwọn ṣe lãrin ile mi. 40 Ati pẹlupẹlu, ti pe ẹnyin ranṣẹ pè awọn ọkunrin lati okẽre wá, sọdọ awọn ti a ranṣẹ pè; si kiyesi i, nwọn de: fun ẹniti iwọ wẹ̀ ara rẹ, ti o si le tirõ, ti o si fi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ li ọṣọ́. 41 Ti o si joko lori àkete daradara, a si tẹ́ tabili siwaju rẹ̀, lori eyi ti iwọ gbe turari mi ati ororó mi lé. 42 Ati ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn pa rọ́rọ wà lọdọ rẹ̀: ati pẹlu enia lasan li a mu awọn Sabeani lati aginjù wá, ti nwọn fi jufù si apá wọn, ati ade daradara si ori wọn. 43 Nigbana ni mo wi fun on ti o gbó ni panṣaga, Nwọn o ha bá a ṣe panṣaga nisisiyi, ati on pẹlu wọn? 44 Sibẹsibẹ wọn wọle tọ̀ ọ, bi nwọn ti iwọle tọ̀ obinrin ti nṣe panṣaga: bẹ̃ni nwọn wọle tọ̀ Ahola ati Aholiba, awọn onifẹkufẹ obinrin. 45 Ati awọn ọkunrin olododo, nwọn o ṣe idajọ wọn, bi a ti iṣe idajọ awọn àgbere obinrin, ati bi a ti iṣe idajọ awọn obinrin ti o ta ẹjẹ silẹ; nitoripe àgbere ni nwọn, ẹjẹ si wà lọwọ wọn. 46 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ẹgbẹ kan tọ̀ wọn wá, emi o si fi wọn fun wọn lati kó wọn lọ, ati lati bà wọn jẹ. 47 Ẹgbẹ na yio si sọ wọn li okuta, nwọn o si fi idà pa wọn; nwọn o pa awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, nwọn o si fi iná kun ile wọn. 48 Bayi li emi o jẹ ki ìwa ifẹkufẹ mọ lãrin ilẹ na, ki a ba le kọ́ gbogbo obinrin, ki nwọn má bà ṣe bi ifẹkufẹ nyin. 49 Nwọn o si san ẹ̀san ìwa ifẹkufẹ nyin si ori nyin, ẹnyin o si rù ẹ̀ṣẹ oriṣa nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.

Esekieli 24

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, li ọdun kẹsan, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, wipe, 2 Ọmọ enia, iwọ kọ orukọ ọjọ na, ani ọjọ kanna yi: ọba Babiloni doju kọ Jerusalemu li ọjọ kanna yi: 3 Si pa owe si ọlọtẹ ilẹ na, si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Gbe ìkoko ka iná, gbe e kà a, si dà omi sinu rẹ̀ pẹlu: 4 Kó aján na jọ sinu rẹ̀, olukuluku aján ti o tobi, itan, ati apá, fi egungun ti o jọju kún inu rẹ̀. 5 Mu ninu agbo-ẹran ti o jọju, ko awọn egungun sabẹ rẹ̀, si jẹ ki o hó dãdã, si jẹ ki nwọn bọ̀ egungun rẹ̀ ninu rẹ̀. 6 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbé ni fun ilu ẹlẹjẹ na, fun ìkoko ti ifõfo rẹ̀ wà ninu rẹ̀, ti ifõfo rẹ̀ kò dá loju rẹ̀: mu u jade li aján li aján; máṣe dìbo nitori rẹ̀. 7 Nitori ẹjẹ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, o gbé e kà ori apata kan, kò tú u dà sori ilẹ, lati fi erupẹ bò o. 8 Ki o ba lè jẹ ki irúnu ki o de, lati gbẹsan; mo ti gbe ẹjẹ rẹ̀ kà ori apata kan, ki a má ba le bò o. 9 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbe ni fun ilu ẹlẹjẹ na! Emi o tilẹ jẹ ki òkiti iná na tobi. 10 Ko igi jọ si i, ko iná jọ, jo ẹran na, fi turari dùn u; si jẹ ki egungun na jona. 11 Si gbe e kà ori ẹyín iná na lasan, ki idẹ rẹ̀ le gbona, ki o le pọ́n, ati ki ẽri rẹ̀ le di yiyọ́ ninu rẹ̀, ki ifõfo rẹ̀ le run. 12 On ti fi eke dá ara rẹ̀ lagara, ifõfo nla rẹ̀ kò si jade kuro lara rẹ̀ ifõfo rẹ̀ yio wà ninu iná. 13 Ninu ẽri rẹ̀ ni iwà ifẹkufẹ wà: nitori mo ti wẹ̀ ọ, iwọ kò si mọ́, a kì yio si tun wẹ̀ ọ kuro ninu ẽri rẹ mọ, titi emi o fi jẹ ki irúnu mi ba le ọ lori. 14 Emi Oluwa li o ti sọ ọ, yio si ṣẹ, emi o si ṣe e: emi kì yio pada sẹhìn, bẹ̃ni emi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ronupiwada; gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati gẹgẹ bi iṣe rẹ ni nwọn o da ọ lẹjọ, li Oluwa Ọlọrun wi. 15 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 16 Ọmọ enia, kiye si i, mo mu ifẹ oju rẹ kuro lọdọ rẹ, nipa lilù kan: ṣugbọn iwọ kò gbọdọ gbãwẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọkun, bẹ̃ni omije rẹ kò gbọdọ ṣan silẹ. 17 Máṣe sọkun, máṣe gbãwẹ fun okú, wé lawàni sori rẹ, si bọ̀ bata rẹ si ẹsẹ rẹ, máṣe bò ète rẹ, máṣe jẹ onjẹ enia. 18 Bẹ̃ni mo sọ fun awọn enia li owurọ: li aṣálẹ obinrin mi si kú, mo si ṣe li owurọ bi a ti pá a li aṣẹ fun mi. 19 Awọn enia si sọ fun mi wipe, Iwọ kì yio ha sọ fun wa ohun ti nkan wọnyi jasi fun wa, ti iwọ ṣe bayi? 20 Mo si da wọn lohùn pe, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe, 21 Sọ fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, kiyesi i emi o sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, titayọ agbara nyin, ifẹ oju nyin, ikãnu ọkàn nyin, ati ọmọ nyin ọkunrin ati ọmọ nyin obinrin, ti ẹnyin ti fi silẹ, yio ti ipa idà ṣubu. 22 Ẹnyin o si ṣe bi emi ti ṣe: ẹnyin kò ni bò ète nyin, bẹ̃ni ẹ kò ni jẹ onjẹ enia. 23 Lawani nyin yio si wà li ori nyin, ati bàta nyin li ẹsẹ nyin: ẹnyin kò ni gbãwẹ, bẹ̃ni ẹ kò ni sọkun: ṣugbọn ẹnyin o ma joro nitori aiṣedẽde nyin, ẹ o si ma ṣọ̀fọ ẹnikan si ẹnikeji. 24 Bayi ni Esekieli jẹ àmi fun nyin: gẹgẹ bi gbogbo ohun ti o ṣe, li ẹ o si ṣe nigbati eyi bá si de, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun: 25 Pẹlupẹlu, iwọ ọmọ enia, kì yio ha ṣe pe, ni ijọ na nigbati mo ba gbà agbara wọn, ayọ̀ ogo wọn, ifẹ oju wọn, ati eyiti nwọn gbe ọkàn wọn le, ọmọ wọn ọkunrin, ati ọmọ wọn obinrin, kuro lọdọ wọn, 26 Ti ẹniti ti o ba sálà nijọ na, yio tọ̀ ọ wá, lati jẹ ki iwọ ki o fi eti ara rẹ gbọ́? 27 Li ọjọ na li ẹnu rẹ yio ṣi si ẹni ti o sala, iwọ o si sọ̀rọ, iwọ kì yio si yadi mọ: iwọ o si jẹ àmi fun wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 25

1 Ọ̀RỌ Oluwa tún tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, doju kọ awọn ara Ammoni, si sọtẹlẹ si wọn; 3 Si wi fun awọn ara Ammoni pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun: Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti iwọ wipe, Aha, si ibi mimọ́ mi, nigbati o di àilọwọ, ati si ilẹ Israeli, nigbati o di ahoro; ati si ilẹ Juda, nigbati nwọn lọ ni ìgbekun; 4 Kiyesi i, nitorina emi o fi ọ le awọn enia ilà-õrùn lọwọ fun ini, nwọn o si gbe ãfin wọn kalẹ ninu rẹ, nwọn o si ṣe ibugbe wọn ninu rẹ: nwọn o jẹ eso rẹ, nwọn o si mu wàra rẹ. 5 Emi o si sọ Rabba di ibujẹ fun ibakasiẹ, ati awọn ọmọ Ammoni di ibùsun fun agbo-ẹran: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 6 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti iwọ ti pa atẹ́wọ, ti o si ti fi ẹsẹ kì ilẹ, ti o si yọ̀ li ọkàn pẹlu gbogbo aránkan rẹ si ilẹ Israeli: 7 Kiye si i, nitorina, emi o nà ọwọ́ mi le ọ, emi o si fi ọ fun awọn keferi fun ikogun; emi o si ke ọ kuro lãrin awọn enia, emi o si jẹ ki o ṣegbé kuro ninu ilẹ gbogbo: emi o pa ọ run; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 8 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe Moabu ati Seiri wipe, Kiye si i, ile Juda dabi gbogbo awọn keferi; 9 Nitorina, kiye si i, emi o ṣi ìha Moabu kuro lati awọn ilu gbogbo, kuro ninu awọn ilu rẹ̀ ti o wà li àgbegbe rẹ̀, ogo ilẹ na, Bet-jeṣimoti, Baalimeoni, ati Kiri-ataimu, 10 Fun awọn ọmọ ìla-orun, pẹlu awọn ara Ammoni, emi o si fi wọn fun ni ni iní; ki a má ba ranti awọn ara Ammoni lãrin orilẹ-ède mọ. 11 Emi o si mu idajọ ṣẹ si Moabu lara, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 12 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe Edomu ti huwà si ile Juda nipa gbigba ẹsan, o si ti ṣẹ̀ gidigidi, o si gbẹ̀san ara rẹ̀ lara wọn. 13 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi pẹlu yio nawọ mi si Edomu, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀; emi o si sọ ọ di ahoro lati Temani; ati awọn ti Dedani, yio ti ipa idà ṣubu. 14 Emi o si gbe ẹ̀san mi le ori Edomu lati ọwọ́ Israeli enia mi: nwọn o si ṣe ni Edomu gẹgẹ bi ibinu mi, ati gẹgẹ bi irúnu mi; nwọn o si mọ̀ ẹ̀san mi, li Oluwa Ọlọrun wi. 15 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti awọn ara Filistia ti lò ilo ẹsan, ti nwọn si ti fi ọkàn ti o kún fun arankàn gbẹsan, lati pa a run, nitori irira atijọ. 16 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o nà ọwọ́ mi le awọn ara Filistia, emi o si ke awọn ara Keriti kuro, emi o si run awọn iyokù ti eti okun. 17 Emi o si san ẹsan nla lara wọn nipa ibáwi gbigbona; nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa, nigbati emi o gbe ẹsan mi le wọn.

Esekieli 26

1 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣu ikini, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, nitoriti Tire ti sọ̀rọ si Jerusalemu, pe, Aha, a fọ́ eyiti iṣe bode awọn orilẹ-ède: a yi i pada si mi, emi o di kikún, on di ahoro: 3 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke. 4 Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata. 5 Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède. 6 Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 7 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu Nebukadnessari ọba Babiloni, ọba awọn ọba, wá si Tire, lati ariwa, pẹlu ẹṣin, ati kẹkẹ́ ogun, ati ẹlẹṣin, ati ẹgbẹ́, ati enia pupọ. 8 Yio fi idà pa awọn ọmọbinrin rẹ li oko: yio si kọ kũkũ tì ọ, yio si mọ odi tì ọ, yio si gbe apata soke si ọ. 9 Yio si gbe ohun-ẹrọ ogun tì odi rẹ, yio si fi ãke rẹ̀ wó ile-iṣọ́ rẹ lulẹ. 10 Nitori ọ̀pọ awọn ẹṣin rẹ̀ ẽkuru wọn yio bò ọ: odi rẹ yio mì nipa ariwo awọn ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́, ati kẹkẹ́ ogun, nigbati yio wọ̀ inu odi rẹ lọ, gẹgẹ bi enia ti wọ̀ inu ilu ti a fọ́. 11 Pátakò ẹṣin rẹ̀ ni yio fi tẹ̀ gbogbo ìta rẹ mọlẹ: on o fi idà pa awọn enia rẹ, ati ọwọ̀n lile rẹ yio wó lulẹ. 12 Nwọn o si fi ọrọ̀ rẹ ṣe ikogun, ati òwo rẹ ṣe ijẹ ogun; nwọn o si wo odi rẹ lulẹ, nwọn o si bà ile rẹ daradara jẹ: nwọn o si ko okuta rẹ, ati ìti igi-ìkọle rẹ, ati erùpẹ rẹ, dà si ãrin omi. 13 Emi o si mu ariwo orin rẹ dakẹ; ati iró dùru rẹ li a kì yio gbọ́ mọ. 14 Emi o si ṣe ọ bi ori apáta; iwọ o si jẹ ibi lati nà awọ̀n le lori; a kì yio kọ́ ọ mọ: nitori emi Oluwa li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi. 15 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Tire; awọn erekùṣu kì yio ha mì-titi nipa iró iṣubu rẹ, nigbati awọn ti o gbọgbẹ́ kigbe, nigbati a ṣe ipani li ãrin rẹ? 16 Nigbana li awọn ọmọ-alade okun yio sọ̀kalẹ kuro lori itẹ́ wọn, nwọn o si pa aṣọ igunwà wọn tì, nwọn o si bọ́ ẹ̀wu oniṣẹ-ọnà wọn: nwọn o fi ìwariri bò ara wọn; nwọn o joko lori ilẹ, nwọn o si warìri nigba-gbogbo, ẹnu o si yà wọn si ọ. 17 Nwọn o si pohunrere-ẹkun fun ọ, nwọn o si wi fun ọ pe, Bawo li ati pa ọ run, iwọ ti awọn èro okun ti ngbe inu rẹ̀, ilu olokikí, ti o lagbara li okun, on ati awọn ti o gbe inu rẹ̀, ẹniti o mu ẹ̀ru wọn wá sara gbogbo awọn ti o pàra ninu rẹ! 18 Nisisiyi ni awọn erekùṣu yio warìri li ọjọ iṣubu rẹ; nitõtọ, awọn erekùṣu ti o wà ninu okun li a o yọ lẹnu nigba atilọ rẹ. 19 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nigbati emi o sọ ọ di ahoro ilu, gẹgẹ bi ilu wọnni ti a kò gbe inu wọn; nigbati emi o si mu ibú wá sori rẹ, ati omi nla yio si bò ọ. 20 Nigbati emi o bá mu ọ walẹ pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, pẹlu awọn enia igbãni, ti emi o si gbe ọ kà ibi isalẹ ilẹ aiye, ni ibi ahoro igbãni, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò, ki a máṣe gbe inu rẹ mọ́: emi o si gbe ogo kalẹ ni ilẹ awọn alãye; 21 Emi o si ṣe ọ ni ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́: bi a tilẹ wá ọ, sibẹ a kì yio tun ri ọ mọ́, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 27

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Nisisiyi, iwọ ọmọ enia, pohunrere ẹkun fun Tire; 3 Ki o si wi fun Tire pe, Iwọ ti a tẹ̀do si ẹnu-ọ̀na okun, oniṣòwo awọn orilẹ-ède fun ọ̀pọlọpọ erekùṣu, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ Tire, iwọ ti wipe, emi pé li ẹwà. 4 Àlà rẹ wà li ãrin okun, awọn ọ̀mọle rẹ ti mu ẹwà rẹ pé. 5 Nwọn ti fi apako firi ti Seniri kàn gbogbo ọkọ̀ rẹ, nwọn ti mu kedari ti Lebanoni wá lati fi ṣe opó ọkọ̀ fun ọ. 6 Ninu igi oaku ti Baṣani ni nwọn ti fi gbẹ́ àjẹ rẹ; ijoko rẹ ni nwọn fi ehin-erin ṣe pelu igi boksi lati erekuṣu Kittimu wá. 7 Ọ̀gbọ daradara iṣẹ-ọnà lati Egipti wá li eyiti iwọ ta fi ṣe igbokun rẹ; aṣọ aláro ati purpili lati erekusu Eliṣa wá li eyiti a fi bò ọ. 8 Awọn ara ilu Sidoni ati Arfadi ni awọn ara ọkọ̀ rẹ̀: awọn ọlọgbọn rẹ, Iwọ Tire, ti o wà ninu rẹ, li awọn atọkọ̀ rẹ. 9 Awọn àgba Gebali, ati awọn ọlọgbọn ibẹ̀, wà ninu rẹ bi adikọ̀ rẹ: gbogbo ọkọ̀ òkun pẹlu awọn ara ọkọ̀ wọn wà ninu rẹ lati ma ṣòwo rẹ. 10 Awọn ti Persia, ati ti Ludi, ati ti Futi, wà ninu ogun rẹ, awọn ologun rẹ: nwọn fi apata ati ìbori-ogun kọ́ ninu rẹ; nwọn fi ẹwà rẹ hàn. 11 Awọn enia Arfadi, pẹlu awọn ogun rẹ, wà lori odi rẹ yika, ati awọn akọ-jamã wà ni ile-iṣọ rẹ: nwọn fi apata kọ́ sara odi rẹ yika; nwọn ti ṣe ẹwà rẹ pé. 12 Tarṣiṣi ni oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ; pẹlu fadakà, irin, tánganran, ati ojé, nwọn ti ṣòwo li ọja rẹ. 13 Jafani, Tubali, ati Meṣeki, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn ti fi ẹrú ati ohun-elò idẹ ṣòwo li ọjà rẹ. 14 Awọn ti ile Togarma fi ẹṣin, ati ẹlẹṣin ati ibaka ṣòwo li ọjà rẹ. 15 Awọn enia Dedani li awọn oniṣòwo rẹ; ọ̀pọlọpọ erekuṣu ni mba ọ ṣòwo, nwọn mu ehin-erin ati igi eboni wá fun ọ lati rà. 16 Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate. 17 Juda, ati ilẹ Israeli, awọn li awọn oniṣòwo rẹ, alikama ti Minniti, ati Pannagi, ati oyin, ati ororo, ati balmu, ni nwọn fi ná ọjà rẹ. 18 Damasku li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ ohun ọjà ti o ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ ọrọ̀; ni ọti-waini ti Helboni, ati irun agutan funfun. 19 Dani pẹlu ati Jafani lati Usali ngbé ọjà rẹ: irin didán, kassia, ati kalamu wà li ọjà rẹ. 20 Dedani ni oniṣòwo rẹ ni aṣọ ibori fun kẹkẹ́. 21 Arabia, ati gbogbo awọn ọmọ-alade Kedari, awọn ni awọn oniṣòwo rẹ, ni ọdọ-agutan, ati agbò, ati ewurẹ; ninu wọnyi ni nwọn ṣe oniṣòwo rẹ. 22 Awọn oniṣòwo Ṣeba ati Rama, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn tà onirũru turari daradara li ọjà rẹ, ati pẹlu onirũru okuta oniyebiye, ati wura. 23 Harani, ati Kanneh, ati Edeni, awọn oniṣòwo Ṣeba, Assuru, ati Kilmadi, ni awọn oniṣòwo rẹ. 24 Wọnyi li awọn oniṣòwo rẹ li onirũru nkan, ni aṣọ alaro, ati oniṣẹ-ọnà, ati apoti aṣọ oniyebiye, ti a fi okùn dì, ti a si fi igi kedari ṣe, ninu awọn oniṣòwo rẹ. 25 Awọn ọkọ Tarṣiṣi ni èro li ọjà rẹ: a ti mu ọ rẹ̀ si i, a si ti ṣe ọ logo li ãrin okun. 26 Awọn atukọ̀ rẹ ti mu ọ wá sinu omi nla: ẹfũfu ilà-õrun ti fọ́ ọ li ãrin okun. 27 Ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ, ọjà tità rẹ, awọn atukọ̀ rẹ, ati atọ́kọ̀ rẹ, adikọ̀ rẹ, ati awọn alábarà rẹ, ati gbogbo awọn ologun rẹ, ti o wà ninu rẹ, ati ninu gbogbo ẹgbẹ́ rẹ, ti o wà li ãrin rẹ, yio ṣubu li ãrin okun li ọjọ iparun rẹ. 28 Awọn ilẹ àgbègbe yio mì nitori iró igbe awọn atọkọ̀ rẹ. 29 Gbogbo awọn alajẹ̀, awọn atukọ̀, ati awọn atọ́kọ̀ okun yio sọkalẹ kuro ninu ọkọ̀ wọn, nwọn o duro lori ilẹ. 30 Nwọn o si jẹ ki a gbọ́ ohùn wọn si ọ, nwọn o si kigbe kikoro, nwọn o si kù ekuru sori ara wọn, nwọn o si yi ara wọn ninu ẽru: 31 Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò. 32 Ati ninu arò wọn ni nwọn o si pohùnrére ẹkún fun ọ, nwọn o si pohùnrére ẹkún sori rẹ, wipe, Ta li o dabi Tire, eyiti a parun li ãrin okun? 33 Nigbati ọjà-tità rẹ ti okun jade wá, iwọ tẹ́ orilẹ-ède pupọ lọrun; iwọ fi ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ, ati ọjà rẹ, sọ awọn ọba aiye di ọlọrọ̀. 34 Nisisiyi ti okun fọ́ ọ bajẹ̀ ninu ibú omi, nitorina òwo rẹ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ li ãrin rẹ, li o ṣubu. 35 Ẹnu yio yà gbogbo awọn olugbe erekuṣu wọnni si ọ, awọn ọba wọn yio si dijì, iyọnu yio yọ li oju wọn. 36 Awọn oniṣòwo lãrin awọn orilẹ-ède yio dún bi ejò si ọ; iwọ o si jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.

Esekieli 28

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun. 3 Wo o, iwọ sa gbọn ju Danieli lọ; kò si si ohun ikọ̀kọ ti o le fi ara sin fun ọ. 4 Ọgbọ́n rẹ ati oye rẹ li o fi ni ọrọ̀, o si ti ni wura ati fadáka sinu iṣura rẹ: 5 Nipa ọgbọ́n rẹ nla ati nipa òwo rẹ li o ti fi sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ, ọkàn rẹ si gbe soke nitori ọrọ̀ rẹ. 6 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti o ti ṣe ọkàn rẹ bi ọkàn Ọlọrun; 7 Kiyesi i, nitorina emi o mu alejo wá ba ọ, ẹlẹ̀ru ninu awọn orilẹ-ède: nwọn o si fà idà wọn yọ si ẹwà ọgbọ́n rẹ, nwọn o si bà didán rẹ jẹ. 8 Nwọn o mu ọ sọkalẹ wá sinu ihò, iwọ o si kú ikú awọn ti a pa li ãrin okun. 9 Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ. 10 Iwọ o kú ikú awọn alaikọlà lọwọ awọn alejo: nitori emi li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi. 11 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, 12 Ọmọ enia, pohùnréré sori ọba Tire, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi dí iye na, o kún fun ọgbọ́n, o si pé li ẹwà. 13 Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ. 14 Iwọ ni kerubu ti a nà ti o si bò; emi si ti gbe ọ kalẹ: iwọ wà lori oke mimọ́ Ọlọrun; iwọ ti rìn soke rìn sodò lãrin okuta iná. 15 Iwọ pé li ọnà rẹ lati ọjọ ti a ti dá ọ, titi a fi ri aiṣedẽde ninu rẹ. 16 Nitori ọ̀pọlọpọ òwo rẹ, nwọn ti fi iwà-ipa kún ãrin rẹ, iwọ si ti ṣẹ̀: nitorina li emi o ṣe sọ ọ nù bi ohun ailọ̀wọ kuro li oke Ọlọrun: emi o si pa ọ run, iwọ kerubu ti o bò, kuro lãrin okuta iná. 17 Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ. 18 Iwọ ti bà ibi mimọ́ rẹ jẹ nipa ọ̀pọlọpọ aiṣedẽde rẹ, nipa aiṣedẽde òwo rẹ; nitorina emi o mu iná jade lati ãrin rẹ wá, yio jó ọ run, emi o si sọ ọ di ẽru lori ilẹ loju gbogbo awọn ti o wò ọ: 19 Gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ lãrin awọn orilẹ-ède li ẹnu o yà si ọ: iwọ o jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai. 20 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 21 Ọmọ enia, gbé oju rẹ si Sidoni, ki o si sọtẹlẹ si i, 22 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Sa wò o, Emi doju kọ ọ, iwọ Sidoni; a o si ṣe mi logo li ãrin rẹ, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o bá ti mu idajọ mi ṣẹ ninu rẹ̀, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu rẹ̀. 23 Emi o si rán àjakálẹ àrun sinu rẹ̀, ati ẹjẹ ni igboro rẹ̀; a o si fi idà pa awọn si a ṣá li ọgbẹ li ãrin rẹ̀ lori rẹ̀ nihà gbogbo; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 24 Kì yio si si ẹgún ti ngún ni fun ile Israeli mọ́, tabi ẹgún bibani ninu jẹ́ ti gbogbo awọn ti o yi wọn ká, ti o si ṣãtá wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun. 25 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nigbati emi o bá ti kó ile Israeli jọ kuro lãrin awọn orilẹ-ède ti a tú wọn ká si, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu wọn loju awọn keferi, nigbana ni nwọn o gbé ilẹ wọn ti mo ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi. 26 Nwọn o si ma gbé inu rẹ̀ ni ibalẹ-aiya, nwọn o si kọ́ ile, nwọn o si gbìn ọgbà àjara; nitõtọ, nwọn o wà ni ibalẹ-aiya, nigbati emi bá ti mu idajọ mi ṣẹ si ara awọn ti ngàn wọn yi wọn kakiri, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn.

Esekieli 29

1 LI ọdun kẹwa, li oṣù kẹwa, li ọjọ kejila oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Farao ọba Egipti, si sọtẹlẹ si i, ati si gbogbo Egipti: 3 Sọ̀rọ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi doju kọ ọ; Farao ọba Egipti, dragoni nla ti o dubulẹ li ãrin awọn odò rẹ̀, eyiti o ti wipe, Ti emi li odò mi, emi li o si ti wà a fun ara mi. 4 Ṣugbọn emi o fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si jẹ ki ẹja odò rẹ ki o lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ, emi o si mu ọ kuro li ãrin odò rẹ, ati gbogbo ẹja odò rẹ yio lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ. 5 Emi o si sọ ọ nù si aginjù, iwọ ati gbogbo ẹja odò rẹ: iwọ o ṣubu ni gbangba oko: a kì yio si kó ọ jọ, bẹ̃li a kì yio si ṣà ọ jọ: emi ti fi ọ ṣe onjẹ fun awọn ẹranko igbẹ́, ati fun awọn ẹiyẹ oju ọrun. 6 Gbogbo awọn olugbé Egipti yio mọ̀ pe emi li Oluwa, nitori nwọn ti jẹ́ ọpá ìye fun ile Israeli. 7 Nigbati nwọn di ọ lọwọ mu, iwọ fọ́, o si ya gbogbo èjiká wọn: nigbati nwọn si fi ara tì ọ, iwọ ṣẹ́, o si mu gbogbo ẹgbẹ́ wọn gbọ̀n. 8 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, emi o mu idà kan wá sori rẹ, ti yio ké enia ati ẹranko kuro ninu rẹ. 9 Ilẹ Egipti yio si di aginjù yio si di ahoro; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitori ti o ti wipe, Odò na temi ni, emi li o si ti wà a. 10 Nitorina, kiyesi i, emi dojukọ ọ, mo si dojukọ odò rẹ, emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro patapata, lati Migdoli lọ de Siene ati titi de ẹkùn Etiopia. 11 Ẹsẹ enia kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni ẹsẹ ẹrankẹran kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio tẹ̀ ẹ dó li ogoji ọdun. 12 Emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ati ilu rẹ̀ yio si di ahoro li ãrin awọn ilu ti o di ahoro li ogoji ọdun: emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin gbogbo orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin gbogbo ilẹ. 13 Ṣugbọn bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Lẹhin ogoji ọdun li emi o ko awọn ara Egipti jọ lati ọdọ awọn enia nibiti a ti tú wọn ká si: 14 Emi o si tun mu igbèkun Egipti pada bọ̀, emi o si mu wọn pada si ilẹ Patrosi, si ilẹ ibí wọn, nwọn o si wà nibẹ bi ijọba ti a rẹ̀ silẹ. 15 Yio si jẹ ijọba ti o rẹ̀lẹ jù ninu awọn ijọba; bẹ̃ni kì yio si gbe ara rẹ̀ ga mọ́ sori awọn orilẹ-ède: nitori emi o dín wọn kù, ti nwọn kì yio fi ṣe olori awọn orilẹ-ède mọ́. 16 Kì yio si jẹ igbẹkẹle fun ile Israeli mọ́, ti o mu aiṣedẽde wọn wá si iranti, nigbati nwọn o ba wò wọn: ṣugbọn nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun. 17 O si ṣe li ọdun kẹtadilọgbọ̀n, li oṣù ikini, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 18 Ọmọ enia, Nebukadresari ọba Babiloni mu ki ogun rẹ̀ sìn irú nla si Tire: gbogbo ori pá, ati gbogbo èjiká bó: sibẹsibẹ on, ati awọn ogun rẹ̀, kò ri owo ọ̀ya gbà, lati Tire fun irú ti o ti sìn si i: 19 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ilẹ Egipti fun Nebukadresari ọba Babiloni; yio si kó awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ati ikógun rẹ̀, ati ijẹ rẹ̀; yio si jẹ owo ọ̀ya fun awọn ogun rẹ̀. 20 Mo ti fi ilẹ Egipti fun u, fun irú ti o sìn si i, nitoriti nwọn ṣiṣẹ́ fun mi, li Oluwa Ọlọrun wi. 21 Li ọjọ na li emi o mu ki iwọ Israeli rú jade, emi o si fun ọ ni iṣínu li ãrin wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 30

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, sọtẹlẹ ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ wu, Egbé fun ọjọ na! 3 Nitori ọjọ na sunmọ tosí, ani ọjọ Oluwa sunmọ tosi, ọjọ ikũkũ ni; yio jẹ akoko ti awọn keferi. 4 Idà yio si wá sori Egipti, irora nla yio wà ni Etiopia, nigbati awọn ti a pa yio ṣubu ni Egipti, nwọn o si mu ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ lọ kuro, ipilẹ rẹ̀ yio si wó lulẹ. 5 Etiopia, ati Libia, ati Lidia, ati gbogbo awọn olùranlọ́wọ, ati Kubu, ati awọn enia ilẹ na ti o mulẹ yio ti ipa idà ṣubu pẹlu wọn. 6 Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi. 7 Nwọn o si di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ilu rẹ̀ yio si wà li àrin awọn ilu ti o di ahoro. 8 Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo bá gbe iná kalẹ ni Egipti, ti gbogbo awọn olùranlọ́wọ rẹ̀ bá parun. 9 Li ọjọ na ni onṣẹ yio lọ lati ọdọ mi ninu ọkọ̀, lati dẹ̀ruba Etiopia ti o wà li alafia, irora yio wá sori wọn gẹgẹ bi li ọjọ Egipti: kiyesi i, o de. 10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si ṣe ki ọ̀pọlọpọ enia Egipti ki o ti ipa ọwọ́ Nebukaddressari ọba Babiloni dínkù. 11 On ati enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹ̀ru awọn orilẹ-ède, li a o mu wá pa ilẹ na run: nwọn o si fà idà wọn yọ si Egipti, nwọn o si fi awọn ti a pa kún ilẹ na. 12 Emi o mu gbogbo odò wọn gbẹ, emi o si tà ilẹ na si ọwọ́ awọn enia buburu; emi o si ti ipa ọwọ́ awọn alejo sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹkún rẹ̀: Emi Oluwa li o ti sọ ọ. 13 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti. 14 Emi o si sọ Patrosi di ahoro, emi o si gbe iná kalẹ ni Soani, emi o si mu idajọ ṣẹ ni No. 15 Emi o si dà irúnu mi si ori Sini, agbara Egipti; emi o si ké ọ̀pọlọpọ enia No kuro. 16 Emi o si gbe iná kalẹ ni Egipti, Sini yio ni irora nla, a o si fà No ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, Nofi yio si ni ipọnju lojojumọ. 17 Awọn ọdọmọkunrin Afeni ati Pibeseti yio ti ipa idà ṣubu: ati awọn wọnyi yio lọ si igbèkun. 18 Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun. 19 Bayi li emi o mu idajọ ṣẹ ni Egipti: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 20 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kini, li ọjọ keje oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 21 Ọmọ enia, emi ti ṣẹ apá Farao ọba Egipti; si kiyesi i, a kì yio dì i ki o ba le san, bẹ̃ni a kì yio fi igi si i lati dì i ki o ba lagbara lati di idà mu. 22 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, emi dojukọ Farao ọba Egipti, emi o si ṣẹ́ apá rẹ̀, eyi ti o le, ati eyiti o ṣẹ́; emi o si jẹ ki idà bọ́ kuro li ọwọ́ rẹ̀. 23 Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin ilẹ. 24 Emi o si mu apá ọba Babiloni le, emi o si fi idà mi si ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn emi o ṣẹ́ apá Farao, yio si ma kerora niwaju rẹ bi ikérora ọkunrin ti a ṣá li aṣápa. 25 Ṣugbọn emi o mu apá ọba Babiloni le, apá Farao yio si rọ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ba fi idà mi si ọwọ́ ọba Babiloni, ki o le ba nà a sori ilẹ Egipti. 26 Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin awọn ilẹ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 31

1 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kẹta, li ọjọ ekini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, sọ fun Farao ọba Egipti, ati fun ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ pe, Tani iwọ jọ ni titobi rẹ? 3 Kiyesi i, awọn ara Assiria ni igi kedari ni Lebanoni ti o li ẹ̀ka daradara, ti o si ṣiji boni, ti o si ga, ṣonṣo ori rẹ̀ si wà lãrin awọn ẹ̀ka bibò. 4 Omi sọ ọ di nla, ibú gbé e ga soke, o fi awọn odò nla rẹ̀ yi oko rẹ̀ ka, o si rán awọn odo kékèké rẹ̀ si gbogbo igbẹ́. 5 Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade. 6 Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe. 7 Bayi li o ni ẹwà ninu titobi rẹ̀, ninu gigùn ẹ̀ka rẹ̀: nitori ti egbò rẹ̀ wà li ẹbá omi nla. 8 Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀. 9 Emi ti ṣe e ni ẹwà nipa ọ̀pọlọpọ ẹ̀ka rẹ̀: tobẹ̃ ti gbogbo igi Edeni, ti o wà ninu ọgbà Ọlọrun, ṣe ilara rẹ̀. 10 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti on gbe ara rẹ̀ soke ni giga, o si ti yọ ṣonṣo rẹ̀ soke lãrin awọn ẹ̀ka didí, ọkàn rẹ̀ si gbe soke nitori giga rẹ̀; 11 Nitorina li emi ti ṣe fi i le alagbara awọn keferi lọwọ; on o bá a ṣe dajudaju: Emi ti lé e jade nitori buburu rẹ̀. 12 Ati awọn alejo, ẹlérù awọn orilẹ-ède, ti ké e kuro, nwọn si ti tú u ká; ẹka rẹ̀ ṣubu sori awọn oke, ati ninu gbogbo afonifoji, ẹka rẹ̀ si ṣẹ́ lẹba gbogbo odò ilẹ na; gbogbo awọn orilẹ-ède aiye si jade lọ kuro labẹ òjiji rẹ̀, nwọn si fi i silẹ. 13 Gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun yio ma gbe ori ahoro rẹ̀, ati lori ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ yio wà. 14 Nitori ki igikigi ti o wà lẹba omi ki o má ba gbe ara wọn ga nitori giga wọn, tabi ki nwọn yọ ṣonṣo wọn lãrin ẹ̀ka dídi; tabi ki igi wọn duro ni giga wọn, gbogbo awọn ti o mu omi: nitori ti a fi gbogbo wọn le ikú lọwọ, si isalẹ aiye, li ãrin awọn ọmọ enia, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò. 15 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pe, Li ọjọ ti o sọkalẹ lọ si ibojì mo jẹ ki ọ̀fọ ki o wà, mo fi ibú bò o mọlẹ, mo si se awọn iṣàn omi, awọn omi nla ni mo si dá duro: emi si jẹ ki Lebanoni ki o ṣọ̀fọ fun u, gbogbo igi igbẹ́ si dakú nitori rẹ̀. 16 Emi mu awọn orilẹ̀-èdè mì nipa iró iṣubu rẹ̀, nigbati mo sọ ọ sinu ipòokú, pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, ati gbogbo igi Edeni, awọn àṣayan ati awọn ti o dara jù ti Lebanoni, gbogbo awọn ti o mu omi, li a o tù ninu ni ìsalẹ aiye. 17 Awọn pẹlu sọkalẹ lọ sinu ipò-okú pẹlu rẹ̀ sọdọ awọn ti a fi idà pa; awọn ti o si jẹ apá rẹ̀, ti ngbe abẹ òjiji rẹ̀ li ãrin awọn keferi. 18 Tani iwọ jọ li ogo ati ni titobi lãrin awọn igi Edeni? sibẹ a o mu ọ wá ilẹ pẹlu awọn igi Edeni si ìsalẹ aiye, iwọ o dubulẹ li ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa. Eyi ni Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 32

1 O si ṣe li ọdun kejila, li oṣù kejila, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, pohunrére fun Farao ọba Egipti, si wi fun u pe, Iwọ dabi ẹgbọ̀rọ kiniun awọn orilẹ-ède, iwọ si dabi dragoni ninu okun, iwọ si jade wá pẹlu awọn odò rẹ, iwọ ti fi ẹsẹ rẹ rú omi, o si ti bà awọn odò wọn jẹ́. 3 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitorina emi o nà àwọn mi sori rẹ pẹlu ẹgbẹ́ enia pupọ̀; nwọn o si fà ọ goke ninu àwọn mi. 4 Nigbana ni emi o fi ọ silẹ lori ilẹ, emi o gbe ọ sọ sinu igbẹ́, emi o mu ki gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun ba le ọ lori, emi o si fi ọ bọ́ gbogbo awọn ẹranko aiye. 5 Emi o gbe ẹran ara rẹ kà awọn ori oke, gbogbo afonifoji li emi o fi giga rẹ kún. 6 Emi o si fi ẹ̀jẹ rẹ rin ilẹ nibiti iwọ nluwẹ́, ani si awọn oke; awọn odò yio si kún fun ọ. 7 Nigbati emi o ba mú ọ kuro, emi o bò ọrun, emi o si mu ki awọn ìrawọ inu rẹ̀ ṣokùnkun, emi o fi kũkũ bò õrùn, òṣupa kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn. 8 Gbogbo imọlẹ oju ọrun li emi o mu ṣokùnkun lori rẹ, emi o gbe okùnkun kà ilẹ rẹ, li Oluwa Ọlọrun wi. 9 Emi o si bí ọ̀pọlọpọ enia ninu, nigbati emi o ba mu iparun rẹ wá sãrin awọn orilẹ-ède, si ilẹ ti iwọ kò ti mọ̀ ri. 10 Nitõtọ, emi o mu ki ẹnu yà ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède si ọ, awọn ọba wọn yio si bẹ̀ru gidigidi nitori rẹ, nigbati emi o ba mì idà mi niwaju wọn; nwọn o si warìri nigbagbogbo, olukuluku enia fun ẹmi ara rẹ̀, li ọjọ iṣubu rẹ. 11 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Idà ọba Babiloni yio wá sori rẹ. 12 Emi o mu ki ọ̀pọlọpọ enia rẹ ṣubu nipa idà awọn alagbara, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ẹ̀de ni gbogbo wọn; nwọn o si bà afẹ́ Egipti jẹ́, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ ni nwọn o parun. 13 Emi o si pa gbogbo awọn ẹranko inu rẹ̀ run kuro lẹba awọn omi nla, bẹ̃ni ẹsẹ enia kì yio rú wọn mọ́ lailai, tabi pátakò awọn ẹranko kì yio rú wọn. 14 Nigbana li emi o mu ki omi wọn ki o rẹlẹ, emi o si mu ki odò wọn ki o ṣàn bi oróro, li Oluwa Ọlọrun wi. 15 Nigbati emi o mu ki ilẹ Egipti di ahoro ti ilẹ na yio si di alaini ohun ti o kún inu rẹ̀ ri, nigbati emi o kọlù gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀, nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa. 16 Eyi ni ohùn-rére, nwọn o si pohùnrére rẹ̀: awọn ọmọbinrin awọn orilẹ-ède yio pohùnrére rẹ̀: nwọn o pohùnrére nitori rẹ̀, ani fun Egipti, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi. 17 O si tun ṣe li ọdun kejila, li ọjọ kẹ̃dogun oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe. 18 Ọmọ enia, pohùnrére fun ọ̀pọlọpọ enia Egipti, ki o si sọ̀ wọn kalẹ, on, ati awọn ọmọbinrin orilẹ-ède olokiki, si ìsalẹ aiye, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò. 19 Tani iwọ julọ li ẹwà? sọkalẹ, ki a si tẹ́ ọ tì awọn alaikọla. 20 Nwọn o ṣubu li ãrin awọn ti a fi idà pa: a fi on le idà lọwọ: fà a, ati awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀. 21 Awọn alagbara lãrin awọn alagbara yio sọ̀rọ si i lati ãrin ipò-okú wá, pẹlu awọn ti o ràn a lọwọ: nwọn sọkalẹ lọ, nwọn dubulẹ, awọn alaikọla ti a fi idà pa. 22 Assuru wà nibẹ̀ ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ wà lọdọ rẹ̀: gbogbo wọn li a pa, ti o ti ipa idà ṣubu: 23 Ibojì awọn ẹniti a gbe kà ẹgbẹ́ ihò, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ si yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti o da ẹ̀ru silẹ ni ilẹ alãye. 24 Elamu wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti nwọn sọkalẹ li alaikọla si ìsalẹ aiye, ti o da ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye; sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò. 25 Nwọn ti gbe akete kan kalẹ fun u li ãrin awọn ti a pa pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka, gbogbo wọn alaikọla ti a fi idà pa: bi a tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye, sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: a fi i si ãrin awọn ti a pa. 26 Meṣeki ati Tubali wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka: gbogbo wọn alaikọlà ti a fi idà pa, bi nwọn tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye. 27 Nwọn kì yio si dubulẹ tì awọn alagbara ti o ṣubu ninu awọn alaikọlà, ti nwọn sọkalẹ lọ si ipò-okú pẹlu ihámọra ogun wọn: nwọn ti fi idà wọn rọ ori wọn, ṣugbọn aiṣedẽde wọn yio wà lori egungun wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ẹ̀ru awọn alagbara ni ilẹ alãye. 28 Lõtọ, a o fọ́ ọ lãrin awọn alaikọlà, iwọ o si dubulẹ tì awọn ti a fi idà pa. 29 Edomu wà nibẹ, awọn ọba rẹ̀, ati awọn ọmọ-alade rẹ̀, ti a tẹ́ pẹlu agbara wọn tì awọn ti a fi idà pa, nwọn o dubulẹ tì awọn alaikọlà, ati pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò. 30 Awọn ọmọ-alade ariwa wà nibẹ, gbogbo wọn, ati awọn ara Sidoni, ti nwọn sọkalẹ lọ pẹlu awọn ti a pa; pẹlu ẹ̀ru wọn, oju agbara wọn tì wọn; nwọn si dubulẹ li alaikọlà pẹlu awọn ti a fi idà pa, nwọn si rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò. 31 Farao yio ri wọn, a o si tù u ninu lori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ani Farao ati gbogbo ogun rẹ̀ ti a fi idà pa, li Oluwa Ọlọrun wi. 32 Nitoriti emi ti dá ẹ̀ru mi silẹ ni ilẹ alãye: a o si tẹ́ ẹ si ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa ani Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 33

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, si wi fun wọn pe, Bi emi bá mu idà wá sori ilẹ kan, bi awọn enia ilẹ na bá mu ọkunrin kan ninu ara wọn, ti nwọn si fi ṣe oluṣọ́ wọn: 3 Bi on bá ri ti idà mbọ̀ wá sori ilẹ na ti o bá fun ipè, ti o si kìlọ fun awọn enia na: 4 Nigbana ẹnikẹni ti o bá gbọ́ iró ipè, ti kò si gbà ìkilọ; bi idà ba de, ti o si mu on kuro, ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori on tikalarẹ̀. 5 O gbọ́ iró ipè, kò si gbà ìkilọ: ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. Ṣugbọn ẹniti o gbọ́ ìkilọ yio gbà ọkàn ara rẹ̀ là. 6 Ṣugbọn bi oluṣọ́ na bá ri ti idà mbọ̀, ti kò si fun ipè, ti a kò si kìlọ fun awọn enia; bi idà ba de, ti o ba si mu ẹnikẹni lãrin wọn, a mu u kuro nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere lọwọ oluṣọ́ na. 7 Bẹ̃ni, iwọ ọmọ enia, emi ti fi ọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli; nitorina iwọ o gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, iwọ o si kìlọ fun wọn lati ọdọ mi. 8 Nigbati emi ba wi fun enia buburu pe, Iwọ enia buburu, kikú ni iwọ o kú, bi iwọ kò bá sọ̀rọ lati kìlọ fun enia buburu na ki o kuro li ọ̀na rẹ̀, enia buburu na yio kú nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ. 9 Ṣugbọn, bi iwọ ba kìlọ fun enia buburu na niti ọ̀na rẹ̀ lati pada kuro ninu rẹ̀, bi on kò ba yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, on o kù nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn iwọ ti gbà ọkàn rẹ là. 10 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun ile Israeli; pe, Bayi li ẹnyin nwi, pe, Bi irekọja ati ẹ̀ṣẹ wa ba wà lori wa, ti awa si njoró ninu wọn, bawo li a o ti ṣe le wà lãye. 11 Sọ fun wọn pe, Bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu, ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀ ki o si yè: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israeli? 12 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ. 13 Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rẹ̀, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rẹ̀ li a kì yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ̀ kú. 14 Ẹ̀wẹ, nigbati emi wi fun enia buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; 15 Bi enia buburu ba mu ògo padà, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrin ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on kì o kú. 16 A kì yio ṣe iranti gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ndá fun u: on ti ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; on o yè nitõtọ. 17 Sibẹ awọn ọmọ enia rẹ wipe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba: ṣugbọn bi o ṣe ti wọn ni, ọ̀na wọn kò dọgba. 18 Nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀ ti o si ṣe aiṣedẽde, on o ti ipa rẹ̀ kú. 19 Ṣugbọn bi enia buburu bá yipada kuro ninu buburu rẹ̀, ti o si ṣe eyiti o tọ ti o si yẹ̀, on o ti ipa rẹ̀ wà lãye. 20 Sibẹ ẹnyin wi pe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba, Ẹnyin ile Israeli, emi o dá olukuluku nyin li ẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀. 21 O si ṣe li ọdun ikejila ikolọ wa, li oṣu kẹwa, li ọjọ karun oṣu, ẹnikan ti o ti salà jade ni Jerusalemu tọ̀ mi wá, o wipe, A kọlù ilu na. 22 Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi li àṣalẹ, ki ẹniti o salà na to de; o si ti ṣi ẹnu mi, titi on fi wá sọdọ mi li owurọ; ẹnu mi si ṣi, emi kò si yadi mọ. 23 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, 24 Ọmọ enia, awọn ti ngbe ahoro ile Israeli wọnni sọ, wipe, Abrahamu jẹ ẹnikan, on si jogun ilẹ na: ṣugbọn awa pọ̀, a fi ilẹ na fun wa ni ini. 25 Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, ẹnyin njẹ ẹ̀jẹ mọ ẹran, ẹ si gbe oju nyin soke si awọn oriṣa nyin, ẹ si ta ẹjẹ silẹ, ẹnyin o ha ni ilẹ na? 26 Ẹnyin gbẹkẹle idà nyin, ẹ ṣe irira, olukuluku nyin bà obinrin aladugbò rẹ̀ jẹ́: ẹnyin o ha ni ilẹ na? 27 Iwọ wi bayi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi emi ti wà, nitõtọ, awọn ti o wà ninu ahoro na yio ti ipa idà ṣubu, ẹniti o si wà ni gbangba oko li emi o si fi fun ẹranko lati pajẹ, awọn ti o si wà ninu odi ati ninu ihò okuta yio ti ipa ajakalẹ-àrun kú. 28 Nitoriti emi o sọ ilẹ na di ahoro patapata, ọ̀ṣọ nla agbara rẹ̀ kì yio si mọ, awọn oke Israeli yio si di ahoro, ti ẹnikan kì yio le là a kọja. 29 Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba ti sọ ilẹ na di ahoro patapata, nitori gbogbo irira ti nwọn ti ṣe. 30 Iwọ ọmọ enia, sibẹ awọn ọmọ enia rẹ nsọ̀rọ si ọ lẹba ogiri ati lẹba ilẹkun ile, ẹnikini si sọ fun ẹnikeji, olukuluku fun arakunrin rẹ̀ wipe, Wá, emi bẹ̀ ọ si gbọ́ ọ̀rọ ti o ti ọdọ Oluwa jade wá. 31 Nwọn si tọ̀ ọ wá, bi enia ti iwá, nwọn si joko niwaju rẹ bi enia mi, nwọn si gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kì yio ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni nwọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkàn wọn tẹ̀le ojukokoro wọn. 32 Si kiyesi i, iwọ jẹ orin ti o dùn pupọ fun wọn, ti ẹnikan ti o ni ohùn daradara, ti o si le fún ohun-elò orin daradara: nitori nwọn gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kò ṣe wọn. 33 Ati nigbati eyi bá ṣẹ, (kiyesi i, yio de,) nigbana ni nwọn o mọ̀ pe wolĩ kan ti wà lãrin wọn.

Esekieli 34

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oluṣọ́ agutan Israeli, sọtẹlẹ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oluṣọ́ agutan; pe, Egbé ni fun awọn oluṣọ́ agutan Israeli, ti mbọ́ ara wọn, awọn oluṣọ́ agutan kì ba bọ́ ọwọ́-ẹran? 3 Ẹnyin jẹ ọrá, ẹ si fi irun agutan bora, ẹ pa awọn ti o sanra: ẹ kò bọ́ agbo-ẹran. 4 Ẹnyin kò mu alailera lara le, bẹ̃ni ẹ kò mu eyiti kò sàn li ara da, bẹ̃ni ẹ kò dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, bẹ̃ni ẹ kò tun mu eyi ti a ti lé lọ padà bọ̀, bẹ̃ni ẹ kò wá eyiti o sọnu, ṣugbọn ipá ati ìka li ẹ ti fi nṣe akoso wọn. 5 A si tú wọn ka, nitori ti oluṣọ́ agutan kò si: nwọn si di onjẹ fun gbogbo ẹranko igbẹ́, nigbati a tú wọn ka. 6 Awọn agutàn mi ṣako ni gbogbo òke, ati lori gbogbo òke kékèké, nitõtọ, a tú ọwọ́-ẹran mi ká ilẹ gbogbo, ẹnikẹni kò bere wọn ki o si wá wọn lọ. 7 Nitorina ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa. 8 Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ, nitori ti ọwọ́-ẹran mi di ijẹ, ti ọwọ́-ẹran mi di onjẹ fun olukuluku ẹranko igbẹ́, nitoriti kò si oluṣọ́ agutan, bẹ̃ni awọn oluṣọ́ agutan kò wá ọwọ́-ẹran mi ri, ṣugbọn awọn oluṣọ́ agutan bọ́ ara wọn, nwọn kò si bọ́ ọwọ́-ẹran mi. 9 Nitorina, ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; 10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ awọn oluṣọ́ agutan; emi o si bere ọwọ́-ẹ̀ran mi lọwọ wọn, emi o si mu wọn dẹ́kun ati ma bọ́ awọn ọwọ́-ẹran: bẹ̃ni awọn ọluṣọ́ agutan kì yio bọ́ ara wọn mọ, nitori ti emi o gbà ọwọ́-ẹran mi kuro li ẹnu wọn ki nwọn ki o má ba jẹ onjẹ fun wọn. 11 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri. 12 Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri. 13 Emi o si mu wọn jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, emi o si kó wọn jọ lati ilẹ gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ara wọn, emi o si bọ́ wọn lori oke Israeli, lẹba odò, ati ni ibi gbigbé ni ilẹ na. 14 Emi o bọ́ wọn ni pápa oko daradara ati lori okè giga Israeli ni agbo wọn o wà: nibẹ ni nwọn o dubulẹ ni agbo daradara, pápa oko ọlọ́ra ni nwọn o si ma jẹ lori oke Israeli. 15 Emi o bọ́ ọwọ́-ẹran mi, emi o si mu ki nwọn dubulẹ, li Oluwa Ọlọrun wi. 16 Emi o wá eyiti o sọnu lọ, emi o si mu eyiti a lé lọ pada bọ̀, emi o si dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, emi o mu eyiti o ṣaisan li ara le; ṣugbọn emi o run eyiti o sanra ati eyiti o lagbara; emi o fi idajọ bọ́ wọn. 17 Bi o ṣe ti nyin, Ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i emi o ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran, lãrin àgbo ati obukọ. 18 Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ? 19 Bi o ṣe ti ọwọ́-ẹran mi ni, nwọn jẹ eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin tẹ̀ mọlẹ; nwọn si mu eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin bajẹ. 20 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi, emi, ani emi, o ṣe idajọ lãrin ọwọ́-ẹran ti o sanra, ati eyiti o rù. 21 Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri. 22 Nitorina ni emi o ṣe gbà ọwọ́-ẹran mi là, nwọn kì yio si jẹ ijẹ́ mọ, emi o si ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran. 23 Emi o si gbe oluṣọ́ agutan kan soke lori wọn, on o si bọ́ wọn, ani Dafidi iranṣẹ mi; on o bọ́ wọn, on o si jẹ oluṣọ́ agutan wọn. 24 Emi Oluwa yio si jẹ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi o jẹ ọmọ-alade li ãrin wọn, emi Oluwa li o ti sọ ọ. 25 Emi o si ba wọn da majẹmu alafia, emi o si jẹ ki awọn ẹranko buburu dasẹ ni ilẹ na: nwọn o si ma gbe aginju li ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó. 26 Emi o si ṣe awọn ati ibi ti o yi oke mi ká ni ibukún; emi o si jẹ ki ojò ki o rọ̀ li akoko rẹ̀, òjo ibukún yio wà. 27 Igi igbẹ́ yio si so eso rẹ̀, ilẹ yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá, nwọn o si wà li alafia ni ilẹ wọn, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ti ṣẹ́ èdídi àjaga wọn, ti emi o si ti gbà wọn lọwọ awọn ti nwọn nsìn bi ẹrú. 28 Nwọn kì yio si ṣe ijẹ fun awọn keferi mọ, bẹ̃ni ẹranko ilẹ na kì yio pa wọn jẹ, ṣugbọn nwọn o wà li alafia ẹnikẹni kì yio si dẹrùba wọn, 29 Emi o si gbe igi okiki kan soke fun wọn, ebi kì yio si run wọn ni ilẹ na mọ, bẹ̃ni nwọn kì yio rù itiju awọn keferi mọ. 30 Bayi ni nwọn o mọ̀ pe emi Oluwa Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, ati awọn, ile Israeli, jẹ enia mi, li Oluwa Ọlọrun wi. 31 Ati ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, ọwọ́-ẹran pápa oko mi ni enia, emi si li Ọlọrun nyin, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 35

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 2 Ọmọ enia, kọ oju rẹ si oke Seiri, ki o si sọtẹlẹ si i. 3 Ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, iwọ oke Seiri, emi dojukọ ọ, emi o nà ọwọ́ mi si ọ, emi o si sọ ọ di ahoro patapata. 4 Emi o sọ awọn ilu rẹ di ahoro, iwọ o si di ahoro, iwọ o si mọ̀ pe, emi li Oluwa. 5 Nitori ti iwọ ti ni irira lailai, iwọ si ti fi awọn ọmọ Israeli le idà lọwọ́, li akoko idãmu wọn, li akoko ti aiṣedẽde wọn de opin. 6 Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi o pèse rẹ silẹ fun ẹ̀jẹ, ẹ̀jẹ yio si lepa rẹ: bi iwọ kò ti korira ẹ̀jẹ nì, ẹ̀jẹ yio lepa rẹ. 7 Bayi li emi o sọ oke Seiri di ahoro patapata, emi o si ké ẹniti nkọja lọ ati ẹniti npadà bọ̀ kuro ninu rẹ̀. 8 Emi o si fi awọn okú rẹ̀ kún awọn oke rẹ̀; ni oke kékèké rẹ, ati ni afonifoji rẹ, ati ni gbogbo odò rẹ li awọn ti a fi idà pa yio ṣubu si. 9 Emi o sọ ọ di ahoro lailai, awọn ilu rẹ kì yio si padà bọ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa. 10 Nitoriti iwọ ti wipe, Awọn orilẹ-ède mejeji yi, ati awọn ilẹ mejeji yi yio jẹ́ ti emi, awa o si ni i; nigbati o ṣepe Oluwa wà nibẹ: 11 Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi emi o tilẹ ṣe gẹgẹ bi ibinu rẹ, ati gẹgẹ bi ilara rẹ ti iwọ ti lò lati inu irira rẹ si wọn; emi o si sọ ara mi di mimọ̀ lãrin wọn, nigbati emi ba ti da ọ li ẹjọ. 12 Iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa, ati pe emi ti gbọ́ ọ̀rọ buburu rẹ, ti iwọ ti sọ si oke Israeli, wipe, A sọ wọn di ahoro, a fi wọn fun wa lati run. 13 Bayi li ẹnyin ti fi ẹnu nyin buná si mi, ẹ si ti sọ ọ̀rọ nyin di pupọ si mi: emi ti gbọ́. 14 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi pe, Nigbati gbogbo aiye nyọ̀, emi o sọ ọ di ahoro. 15 Gẹgẹ bi iwọ ti yọ̀ si ini ile Israeli, nitori ti o di ahoro, bẹ̃li emi o ṣe si ọ; iwọ o di ahoro, iwọ oke Seiri ati gbogbo Idumea, ani gbogbo rẹ̀: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 36

1 ATI iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oke Israeli, si wipe, Ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: 2 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nitori ti ọta ti wi si nyin pe, Aha, ani ibi giga igbãni jẹ tiwa ni ini: 3 Nitorina sọtẹlẹ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Nitõtọ nitori nwọn ti sọ ọ di ahoro, ti nwọn si gbe ọ mì niha gbogbo, ki ẹnyin ba le jẹ ini fun awọn keferi iyokù, ti a mu nyin si ẹnu, ti ẹnyin si jasi ẹ̀gan awọn enia: 4 Nitorina, ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oke-nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, fun ibi idahoro, ati fun awọn ilu ti a kọ̀ silẹ, ti o di ijẹ ati iyọsùtisi fun awọn keferi iyokù ti o yika kiri; 5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitõtọ ninu iná owu mi li emi ti sọ̀rọ si awọn keferi iyokù, ati si gbogbo Idumea, ti o ti fi ayọ̀ inu wọn gbogbo yàn ilẹ mi ni iní wọn, pẹlu àrankan inu, lati ta a nù fun ijẹ. 6 Nitorina sọtẹlẹ niti ilẹ Israeli, ki o si wi fun awọn oke nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Wò o, emi ti sọ̀rọ ninu owu mi, ati ninu irúnu mi, nitori ti ẹnyin ti rù itiju awọn keferi. 7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi ti gbe ọwọ́ mi soke, Nitõtọ awọn keferi ti o yi nyin ka, awọn ni yio rù itiju wọn. 8 Ṣugbọn ẹnyin, oke Israeli, ẹnyin o yọ ẹka jade, ẹ o si so eso nyin fun Israeli enia mi; nitori nwọn fẹrẹ̀ de. 9 Si kiyesi i, emi wà fun nyin, emi o si yipadà si nyin, a o si ro nyin, a o si gbìn nyin: 10 Emi o si mu enia bi si i lori nyin, gbogbo ile Israeli, ani gbogbo rẹ̀: awọn ilu yio si ni olugbe, a o si kọ́ ibi ti o di ahoro: 11 Emi o si mu enia ati ẹranko bi si i lori nyin; nwọn o si pọ̀ si i, nwọn o si rẹ̀: emi o si mu nyin joko ni ibugbe nyin, bi ti atijọ, emi o si ṣe si nyin jù igbà ibẹ̀rẹ nyin lọ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa. 12 Nitõtọ, emi o mu ki enia rìn lori nyin, ani Israeli enia mi; nwọn o si ni ọ, iwọ o si jẹ iní wọn, iwọ kì yio si gbà wọn li ọmọ mọ lati isisiyi lọ. 13 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori nwọn wi fun nyin, pe, Iwọ jẹ enia run, o si ti gbà awọn orilẹ-ède li ọmọ; 14 Nitorina iwọ kì yio jẹ enia run mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio gbà awọn orilẹ rẹ li ọmọ mọ, li Oluwa Ọlọrun wi. 15 Bẹ̃ni emi kì yio mu ki enia gbọ́ ìtiju awọn keferi ninu rẹ mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio rù ẹ̀gan awọn orilẹ-ède mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio mu ki orilẹ-ẹ̀de rẹ ṣubu mọ, li Oluwa Ọlọrun wi. 16 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 17 Ọmọ enia, nigbati ile Israeli ngbe ilẹ ti wọn; nwọn bà a jẹ nipa ọ̀na wọn, ati nipa iṣe wọn: ọ̀na wọn loju mi dabi aimọ́ obinrin ti a mu kuro. 18 Nitorina emi fi irúnu mi si ori wọn, nitori ẹ̀jẹ ti wọn ti ta sori ilẹ na, ati nitori ere wọn ti wọn ti fi bà a jẹ. 19 Emi si ti tú wọn ká sãrin awọn keferi, a si fọn wọn ká si gbogbo ilẹ: emi dá wọn lẹjọ, gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi iṣe wọn. 20 Nigbati awọn si wọ̀ inu awọn keferi, nibiti nwọn lọ, nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ, nigbati nwọn wi fun wọn pe, Awọn wọnyi li enia Oluwa, nwọn si ti jade kuro ni ilẹ rẹ̀. 21 Ṣugbọn ãnu orukọ mimọ́ mi ṣe mi, ti ile Israeli ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ. 22 Nitorina sọ fun ile Israeli, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli, emi kò ṣe eyi nitori ti nyin, ṣugbọn fun orukọ mimọ́ mi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti ẹnyin lọ. 23 Emi o si sọ orukọ nla mi di mimọ́, ti a bajẹ lãrin awọn keferi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin wọn; awọn keferi yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati a o sọ mi di mimọ́ ninu nyin niwaju wọn, li Oluwa Ọlọrun wi. 24 Nitori emi o mu nyin kuro lãrin awọn keferi, emi o si ṣà nyin jọ kuro ni gbogbo ilẹ, emi o si mu nyin padà si ilẹ ti nyin. 25 Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin. 26 Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin. 27 Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn. 28 Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin. 29 Emi o si gbà nyin là kuro ninu aimọ́ nyin gbogbo: emi o si pè ọkà wá, emi o si mu u pọ̀ si i, emi kì yio si mu ìyan wá ba nyin. 30 Emi o si sọ eso-igi di pupọ̀, ati ibísi oko, ki ẹ má bà gbà ẹ̀gan ìyan mọ lãrin awọn keferi. 31 Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin. 32 Kì iṣe nitori ti nyin li emi ṣe eyi, ni Oluwa Ọlọrun wi, ẹ mọ̀ eyi: ki oju ki o tì nyin, ki ẹ si dãmú nitori ọ̀na ara nyin, ile Israeli. 33 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Li ọjọ ti emi o ti wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu aiṣedẽde nyin gbogbo, emi o mu ki a tun gbe ilu, a o si kọ́ ibi ahoro wọnni. 34 Ilẹ ahoro li a o si ro, ti o ti di ahoro li oju gbogbo awọn ti o ti kọja. 35 Nwọn o si wipe, Ilẹ yi ti o ti di ahoro ti dabi ọgbà Edeni; ati ilu ti o tú, ti o di ahoro, ti o si parun, di ilu olodi, o si ni olugbe. 36 Nigbana ni awọn keferi iyokù yika nyin yio mọ̀ pe emi Oluwa ti kọ́ ilu ti o parun, emi si ti gbìn eyiti o ti di ahoro: emi Oluwa ti sọ ọ, emi o si ṣe e. 37 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli yio bere eyi lọwọ mi, lati ṣe e fun wọn, emi o mu enia bi si i fun wọn bi ọwọ́-ẹran. 38 Gẹgẹ bi ọwọ́-ẹran mimọ́, bi ọwọ́-ẹran Jerusalemu ni àse wọn ti o ni ironu, bẹ̃ni ilu ti o di ahoro yio kún fun enia: nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

Esekieli 37

1 ỌWỌ́ Oluwa wà li ara mi, o si mu mi jade ninu ẹmi Oluwa, o si gbe mi kalẹ li ãrin afonifojì ti o kún fun egungun, 2 O si mu mi rìn yi wọn ka: si wò o, ọ̀pọlọpọ ni mbẹ ni gbangba afonifojì; si kiyesi i, nwọn gbẹ pupọpupọ. 3 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi le yè? Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ li o le mọ̀. 4 O tun wi fun mi pe, Sọtẹlẹ sori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, Ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa. 5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ̀ inu nyin, ẹnyin o si yè: 6 Emi o si fi iṣan sara nyin, emi o si mu ẹran wá sara nyin, emi o si fi àwọ bò nyin, emi o si fi ẽmi sinu nyin, ẹnyin o si yè; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 7 Bẹ̃ni mo ṣotẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi: bi mo si ti sọtẹlẹ, ariwo ta, si wò o, mimì kan wà, awọn egungun na si wá ọdọ ara wọn, egungun si egungun rẹ̀. 8 Nigbati mo si wò, kiyesi i, iṣan ati ẹran-ara wá si wọn, àwọ si bò wọn loke: ṣugbọn ẽmi kò si ninu wọn. 9 Nigbana li o sọ fun mi, pe, ọmọ enia, Sọtẹlẹ si ẽmi, sọtẹlẹ, si wi fun ẽmi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ ẽmi, wá lati igun mẹrẹrin, si mí si okú wọnyi, ki nwọn ba le yè. 10 Bẹ̃ni mo sọtẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi, ẽmi na si wá sinu wọn, nwọn si yè, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn ogun nlanla. 11 Nigbana li o sọ fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi ni gbogbo ile Israeli: wò o, nwọn wipe, Egungun wa gbẹ, ireti wa si pin: ni ti awa, a ti ke wa kuro. 12 Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi ibojì nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu ibojì nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israeli. 13 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi bá ti ṣí ibojì nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu ibojì nyin. 14 Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li Oluwa wi. 15 Ọrọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, 16 Ati iwọ, ọmọ enia, mu igi kan, si kọwe si i lara, Fun Juda, ati fun awọn ọmọ Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀: si mu igi miran, si kọwe si i lara, Fun Josefu, igi Efraimu, ati fun gbogbo ile Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀. 17 Si dà wọn pọ̀ ṣọkan si igi kan; nwọn o si di ọkan li ọwọ́ rẹ. 18 Nigbati awọn enia rẹ ba ba ọ sọ̀rọ, wipe, Iwọ kì yio fi idi nkan wọnyi hàn wa? 19 Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu igi Josefu, ti o wà li ọwọ́ Efraimu, ati awọn ẹya Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀, emi o si mu wọn pẹlu rẹ̀, pẹlu igi Juda, emi o si sọ wọn di igi kan, nwọn o si di ọkan li ọwọ́ mi. 20 Igi ti iwọ kọwe si lara yio wà li ọwọ́ rẹ, niwaju wọn. 21 Si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu awọn ọmọ Israeli kuro lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ, emi o si ṣà wọn jọ niha gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ti wọn. 22 Emi o si sọ wọn di orilẹ-ède kan ni ilẹ lori oke-nla Israeli; ọba kan ni yio si jẹ lori gbogbo wọn: nwọn kì yio si jẹ orilẹ-ède meji mọ, bẹ̃ni a kì yio sọ wọn di ijọba meji mọ rara. 23 Bẹ̃ni nwọn kì yio fi oriṣa wọn bà ara wọn jẹ mọ, tabi ohun-irira wọn, tabi ohun irekọja wọn: ṣugbọn emi o gbà wọn là kuro ninu gbogbo ibugbe wọn, nibiti nwọn ti dẹṣẹ, emi o si wẹ̀ wọn mọ́: bẹ̃ni nwọn o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn. 24 Dafidi iranṣẹ mi yio si jẹ ọba lori wọn; gbogbo wọn ni yio si ni oluṣọ-agutan kan: nwọn o rìn ninu idajọ mi pẹlu, nwọn o si kiyesi aṣẹ mi, nwọn o si ṣe wọn. 25 Nwọn o si ma gbe ilẹ ti emi ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi, nibiti awọn baba nyin ti gbe; nwọn o si ma gbe inu rẹ̀, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ ọmọ wọn lailai: Dafidi iranṣẹ mi yio si ma jẹ ọmọ-alade wọn lailai. 26 Pẹlupẹlu emi o ba wọn dá majẹmu alafia; yio si jẹ majẹmu aiyeraiye pẹlu wọn: emi o si gbe wọn kalẹ, emi o si mu wọn rẹ̀, emi o si gbe ibi mimọ́ mi si ãrin wọn titi aiye. 27 Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. 28 Awọn keferi yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ Israeli di mimọ́, nigbati ibi mimọ́ mi yio wà li ãrin wọn titi aiye.

Esekieli 38

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, 2 Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Gogu, ilẹ Magogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali, si sọtẹlẹ si i, 3 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ ọ, iwọ Gogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali: 4 Emi o si dá ọ padà, emi o si fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si mu ọ jade wá, ati gbogbo ogun rẹ, ẹṣin ati ẹlẹṣin, gbogbo wọn li a wọ̀ laṣọ daradara, ani ẹgbẹ́ nla pẹlu apata on asà, gbogbo wọn dì idà mu: 5 Persia, Etiopia, ati Libia pẹlu wọn; gbogbo wọn pẹlu asà on akoro: 6 Gomeri, ati gbogbo ogun rẹ̀; ile Togarma ti ihà ariwa, ati gbogbo ogun rẹ̀: enia pupọ̀ pẹlu rẹ̀. 7 Iwọ mura silẹ, si mura fun ara rẹ, iwọ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ti a gbajọ fun ọ, ki iwọ jẹ alãbo fun wọn. 8 Lẹhìn ọjọ pupọ̀ li a o bẹ̀ ọ wò: li ọdun ikẹhìn, iwọ o wá si ilẹ ti a gbà padà lọwọ idà, ti a si kojọ pọ̀ kuro lọdọ enia pupọ̀, lori oke-nla Israeli, ti iti ma di ahoro: ṣugbọn a mu u jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, nwọn o si ma gbe li ailewu, gbogbo wọn. 9 Iwọ o goke wá, iwọ o si de bi ijì, iwọ o dabi awọsanma lati bò ilẹ, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati ọ̀pọlọpọ enia pẹlu rẹ. 10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; yio si ṣe pe nigbakanna ni nkan yio sọ si ọ̀kàn rẹ, iwọ o si rò èro ibi kan. 11 Iwọ o si wipe, emi o goke lọ si ilẹ ileto ti kò ni odi: emi o tọ̀ awọn ti o wà ni isimi lọ, ti nwọn ngbe laibẹ̀ru, ti gbogbo wọn ngbe laisi odi, ti nwọn kò si ni agbarà-irin tabi ẹnu-odi, 12 Lati lọ kó ikogun, ati lati lọ mu ohun ọdẹ; lati yi ọwọ́ rẹ si ibi ahoro wọnni ti a tẹ̀do nisisiyi, ati si enia ti a kojọ lati inu awọn orilẹ-ède wá, awọn ti o ti ni ohun-ọ̀sin ati ẹrù, ti ngbe oke ilẹ na. 13 Ṣeba, ati Dedani, ati awọn oniṣòwo Tarṣiṣi, pẹlu gbogbo awọn ọmọ kiniun wọn, yio si wi fun ọ pe, Ikogun ni iwọ wá kó? lati wá mu ohun ọdẹ li o ṣe gbá awọn ẹgbẹ́ rẹ jọ? lati wá rù fadaka ati wura lọ, lati wá rù ohun-ọsìn ati ẹrù, lati wá kó ikogun nla? 14 Nitorina, sọtẹlẹ, ọmọ enia, si wi fun Gogu pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ni ijọ na nigbati awọn enia mi Israeli ba ngbe laibẹ̀ru, iwọ kì yio mọ̀? 15 Iwọ o si ti ipò rẹ wá lati iha ariwa, iwọ, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ, gbogbo wọn li o ngùn ẹṣin, ẹgbẹ nla, ati ọ̀pọlọpọ ogun alagbara: 16 Iwọ o si goke wá si awọn enia mi Israeli, bi awọsanma lati bò ilẹ; yio si ṣe nikẹhin ọjọ, emi o si mu ọ dojukọ ilẹ mi, ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ mi, nigbati a o yà mi si mimọ́ ninu rẹ, niwaju wọn, iwọ Gogu. 17 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ li ẹniti mo ti sọ̀rọ rẹ̀ nigba atijọ lati ọwọ́ awọn iranṣẹ mi awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ li ọjọ wọnni li ọdun pupọ pe, emi o mu ọ wá dojukọ wọn? 18 Yio si ṣe nigbakanna li ákoko ti Gogu yio wá dojukọ ilẹ Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, ti irúnu mi yio yọ li oju mi. 19 Nitori ni ijowu mi ati ni iná ibinu mi ni mo ti sọ̀rọ, Nitõtọ li ọjọ na mimì nla kan yio wà ni ilẹ Israeli; 20 Awọn ẹja inu okun, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹranko inu igbó, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, ati gbogbo enia ti mbẹ loju ilẹ, yio si mì niwaju mi, a o si bì òke-nla ṣubu, ati gbogbo ibi giga yio ṣubu, olukuluku ogiri yio ṣubu lulẹ. 21 Emi o si pè idà si i lori gbogbo oke mi, ni Oluwa Ọlọrun wi: idà olukuluku yio si dojukọ arakunrin rẹ̀. 22 Emi o si fi ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ ba a wijọ; emi o si rọ̀ ojò pupọ̀, ati yìnyin nla, iná ati imi-ọjọ, si i lori, ati sori áwọn ẹgbẹ rẹ̀, ati sori ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀. 23 Emi o si gbe ara mi lèke, emi o si ya ara mi si mimọ́; emi o si di mimọ̀ loju ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esekieli 39

1 NITORINA, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ si Gogu, si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi dojukọ́ ọ, iwọ Gogu, olori ọmọ-alade Meṣeki ati Tubali: 2 Emi o si dá ọ padà, emi o si dári rẹ, emi o si mu ọ goke wá lati ihà ariwa, emi o si mu ọ wá sori oke giga Israeli: 3 Emi o si lù ọrun rẹ kurò li ọwọ́ osì rẹ, emi o si mu ọfà rẹ bọ kuro lọwọ ọtun rẹ. 4 Iwọ o ṣubu lori òke giga Israeli, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ: emi o fi ọ fun ẹiyẹ ọdẹ onirũru iyẹ, ati ẹranko igbẹ lati pa jẹ. 5 Iwọ o ṣubu ni gbangba oko: nitori emi li o sọ ọ, ni Oluwa Ọlọrun wi. 6 Emi o si rán iná si Magogu, ati sãrin awọn ti ngbe erekuṣu laibẹ̀ru; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. 7 Emi o si sọ orukọ mimọ́ mi di mimọ̀ lãrin enia mi Israeli; emi kì yio si jẹ ki nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ mọ: awọn orilẹ-ède yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ni Israeli. 8 Kiye si i, o ti de, a si ti ṣe e; ni Oluwa Ọlọrun wi, eyi ni ọjọ ti emi ti sọ. 9 Awọn ti o si ngbe ilu Israeli yio jade lọ, nwọn o si fi ohun ihamọra wọnni jona ati asa ati apata, ọrun ati ọfà, kùmọ ati ọ̀kọ; nwọn o si fi iná sun wọn li ọdun meje: 10 Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi. 11 Yio si ṣe li ọjọ na, emi o fi ibikan fun Gogu nibẹ fun iboji ni Israeli, afonifoji awọn èro ni gabasi okun; on si pa awọn èro ni ẹnu mọ: nibẹ ni nwọn o gbe sin Gogu ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ si: nwọn o si pè e ni, Afonifoji Hamon-gogu. 12 Oṣù meje ni ile Israeli yio si ma fi sin okú wọn, ki nwọn ba le sọ ilẹ na di mimọ́. 13 Gbogbo enia ilẹ na ni yio si sin wọn: yio si jẹ okiki fun wọn li ọjọ ti a o yìn mi logo, ni Oluwa Ọlọrun wi. 14 Nwọn o si yà awọn ọkunrin sọtọ ti yio ma fi ṣe iṣẹ iṣe, lati ma rìn ilẹ na ja lati lọ isin awọn erò ti o kù lori ilẹ, lati sọ ọ di mimọ́: lẹhin oṣù meje nwọn o ma wá kiri. 15 Awọn èro ti nlà ilẹ na kọja, nigbati ẹnikan ba ri egungun enia kan, yio sàmi kan si ẹba rẹ̀, titi awọn asinku yio fi sin i si afonifoji Hamon-gogu. 16 Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́. 17 Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ. 18 Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani. 19 Ẹ o si jẹ ọra li ajẹyo, ẹ o si mu ẹjẹ li amupara, lati inu ẹbọ mi ti mo ti rú fun nyin. 20 Bayi li a o fi ẹṣin ati ẹlẹṣin bọ́ nyin yo lori tabili mi, pẹlu awọn alagbara, ati gbogbo awọn ologun, ni Oluwa Ọlọrun wi. 21 Emi o si gbe ogo mi kalẹ lãrin awọn keferi, gbogbo awọn keferi yio si ri idajọ mi ti mo ti ṣe, ati ọwọ́ mi ti mo ti fi le wọn. 22 Ile Israeli yio si mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun wọn lati ọjọ na lọ titi. 23 Awọn keferi yio si mọ̀ pe Israeli lọ si igbekùn nitori aiṣedẽde wọn: nitoriti nwọn ti ṣọ̀tẹ si mi, nitorina ni mo ṣe fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn, ti mo si fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ: gbogbo wọn si ti ipa idà ṣubu. 24 Gẹgẹ bi aimọ́ wọn, ati gẹgẹ bi irekọja wọn ni mo ṣe si wọn, mo si fi oju mi pamọ́ kuro lọdọ wọn. 25 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nisisiyi li emi o mu igbèkun Jakobu padà bọ̀, emi o si ṣãnu fun gbogbo ile Israeli, emi o si jowu nitori orukọ mi mimọ́: 26 Nwọn o si rù itiju wọn, ati gbogbo ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, nigbati nwọn ngbe laibẹ̀ru ni ilẹ wọn, ti ẹnikẹni kò si dẹ̀ruba wọn. 27 Nigbati emi ti mu wọn bọ̀ lati ọdọ orilẹ-ède, ti mo si ko wọn jọ lati ilẹ awọn ọta wọn wá, ti a si yà mi si mimọ́ ninu wọn niwaju orilẹ-ède pupọ. 28 Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn, nipa kikó ti mo mu ki a kó wọn lọ si igbekun lãrin awọn keferi: ṣugbọn mo ti ṣà wọn jọ si ilẹ wọn, emi kò si fi ẹnikẹni wọn silẹ nibẹ mọ. 29 Emi kì yio si fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn mọ: nitori emi ti tú ẹmi mi sori ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 40

1 LI ọdun kẹ̃dọgbọn oko-ẹrú wa, ni ibẹ̀rẹ ọdun na, li ọjọ ikẹwa oṣù, li ọdun ikẹrinla lẹhin igbati ilu fọ́, li ọjọ na gan, ọwọ́ Oluwa wà lara mi, o si mu mi wá sibẹ na. 2 Ninu iran Ọlọrun li o mu mi wá si ilẹ Israeli, o si gbe mi ka oke giga kan, lori eyiti kikọ ilu wà ni iha gusu. 3 O si mu mi wá sibẹ, si kiyesi i, ọkunrin kan mbẹ, ẹniti irí rẹ̀ dabi irí bàba, pẹlu okùn ọ̀gbọ li ọwọ́ rẹ̀, ati ije iwọ̀nlẹ; on si duro ni ẹnu-ọ̀na. 4 Ọkunrin na si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi oju rẹ wò, ki o si fi eti rẹ gbọ́, ki o si gbe ọkàn rẹ le ohun gbogbo ti emi o fi han ọ; nitori ka ba le fi wọn han ọ li a ṣe mu ọ wá ihinyi: sọ ohun gbogbo ti o ri fun ile Israeli. 5 Si kiye si i, ogiri kan mbẹ lode ile na yika, ije iwọ̀nlẹ kan si mbẹ lọwọ ọkunrin na, igbọnwọ mẹfa, nipa igbọnwọ ati ibú atẹlẹwọ kan: o si wọ̀n ibú ile na, ije kan; ati giga rẹ̀, ije kan. 6 Nigbana li o wá si ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si gùn oke atẹ̀gun na lọ, o si wọ̀n iloro ẹnu ọ̀na, ti o jẹ ije kan ni ibú; ati iloro miran ti ẹnu-ọ̀na na, ti o jẹ ije kan ni ibú. 7 Yará kékèké si jẹ ije kan ni gigùn, ati ije kan ni ibú; ati lãrin yará kékèké igbọnwọ marun; àtẹwọ ẹnu-ọ̀na lẹba iloro ẹnu-ọ̀na ti inu si jẹ ije kan. 8 O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, ije kan. 9 O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na, igbọnwọ mẹjọ; ati atẹrigba rẹ̀, igbọnwọ meji-meji; iloro ti ẹnu-ọ̀na na si mbẹ ninu. 10 Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún. 11 O si wọ̀n ibu abawọle ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹwa; ati gigùn ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹtala. 12 Àye ti si mbẹ niwaju awọn yará kékèké na jẹ igbọnwọ kan nihà ìhin, àye na si jẹ igbọnwọ kan nihá ọhún; awọn yará kékèké na si jẹ igbọnwọ mẹfa nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹfa niha ọhún. 13 O si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na lati orule yará kékèké kan lọ de orule miran: ibú rẹ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn, ilẹkùn dojukọ ilẹkùn. 14 O si ṣe atẹrigba ọlọgọta igbọnwọ, ani titi de atẹrigba àgbalá yi ẹnu-ọ̀na na ka. 15 Lati iwaju ẹnu-ọ̀na àtẹwọ titi fi de iwaju iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, adọta igbọnwọ. 16 Awọn ferese tõro si mbẹ lara yará kékèké na, ati lara atẹrigba wọn ninu ẹnu-ọ̀na niha gbogbo ati pẹlu yará iloro: ferese pupọ si mbẹ niha inu gbogbo: igi ọpẹ si mbẹ lara olukuluku atẹrigbà. 17 O si mu mi wá si agbala ode, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ yará mbẹ nibẹ, a si fi okuta tẹ́ agbala na niha gbogbo: ọgbọ̀n yará ni mbẹ lori okuta itẹlẹ na. 18 Ati okuta itẹlẹ ti iha ẹnu-ọ̀na na ti o kọju si gigun ẹnu-ọ̀na, ani okuta itẹlẹ isalẹ. 19 O si wọ̀n ibú rẹ̀ lati iwaju ẹnu-ọ̀na isalẹ titi fi de iwaju àgbala inu ti ode, ọgọrun igbọnwọ niha ila-õrun ati niha ariwa. 20 Ẹnu-ọ̀na àgbala ode ti o kọju si ariwa, o wọ̀n gigun rẹ̀, ati ibu rẹ̀. 21 Awọn yará kékèké ibẹ̀ jẹ mẹta niha ìhin, mẹta nihà ọhun; awọn atẹrigba ibẹ ati iloro ibẹ jẹ gẹgẹ bi ìwọn ẹnu-ọ̀na ekini: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n. 22 Ati fèrese wọn, ati iloro wọn, ati igi ọpẹ wọn jẹ gẹgẹ bi ìwọn ti ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun; nwọn si ba atẹgun meje gùn oke rẹ̀ lọ; awọn iloro na si mbẹ niwaju wọn. 23 Ati ẹnu-ọ̀na agbala inu ti o kọju si ẹnu-ọ̀na ti ariwa, ati ti ila-õrun; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na, ọgọrun igbọnwọ. 24 O si mu mi lọ si ọ̀na gusù, si kiye si i, ẹnu-ọ̀na kan mbẹ li ọ̀na gusù: o si wọ̀n awọn atẹrigba wọn, ati ìloro wọn gẹgẹ bi ìwọn wọnyi. 25 Fèrese pupọ si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu iloro wọn yika, bi ferese wọnni: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn. 26 Atẹ̀gun meje ni mbẹ lati bá gùn oke rẹ̀, ati awọn iloro rẹ̀ si mbẹ niwaju wọn: o si ni igi ọpẹ, ọkan nihà ìhin, ati ọkan nihà ọhún, lara awọn atẹrigbà rẹ̀. 27 Ati ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu mbẹ li ọ̀na gusu; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na li ọ̀na gusu, ọgọrun igbọnwọ. 28 O si mu mi wá si agbalá ti inu nipa ẹnu-ọ̀na gusu: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na gusu na gẹgẹ bi ìwọn wọnyi; 29 Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú. 30 Awọn iloro ti mbẹ yika jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni ibú. 31 Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀: abágòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ. 32 O si mu mi wá si agbalá ti inu nihà ọ̀na ila-õrun: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na, gẹgẹ bi iwọn wọnyi. 33 Ati yara kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, jẹ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu awọn iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, ati igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú. 34 Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀, nihà ìhin, ati nihà ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ. 35 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ariwa, o si wọ̀n ọ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi; 36 Awọn yará kékèké rẹ̀, atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, ati ferese rẹ̀ yika: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n. 37 Ati atẹrigba rẹ̀ mbẹ niha agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigba rẹ̀, niha ìhin, ati niha ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ. 38 Ati yàra ati abáwọle rẹ̀ wà nihà atẹrigbà ẹnu-ọ̀na na, nibiti nwọn ima wẹ̀ ọrẹ ẹbọ sisun. 39 Ati ni iloro ẹnu-ọ̀na na tabili meji mbẹ nihà ìhin, ati tabili meji nihà ọ̀hun, lati ma pa ẹran ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja lori wọn. 40 Ati ni ihà ode, bi a ba nlọ si àbáwọle ẹnu-ọ̀na ariwa, ni tabili meji mbẹ; ati nihà miran, ti iṣe iloro ẹnu-ọ̀na, ni tabili meji mbẹ. 41 Tabili mẹrin mbẹ nihà ìhin, tabili mẹrin si mbẹ nihà ọ̀hun, nihà ẹnu-ọ̀na; tabili mẹjọ, lori eyiti nwọn a ma pa ẹran ẹbọ wọn. 42 Tabili mẹrin na si jẹ ti okuta gbigbẹ́ fun ọrẹ ẹbọ sisun, igbọnwọ kan on ãbọ ni gigùn, ati igbọnwọ kan on ãbọ ni ibú, ati igbọnwọ kan ni giga: lori eyiti nwọn a si ma kó ohun-elò wọn le, ti nwọn ifi pa ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹran ẹbọ. 43 Ati ninu ni ìwọ ẹlẹnu meji, oníbu atẹlẹwọ kan, ti a kàn mọ ọ yika: ati lori awọn tabili na ni ẹran ọrẹ gbe wà. 44 Ati lode ẹnu-ọ̀na ti inu ni yará awọn akọrin gbe wà, ninu agbala ti inu, ti mbẹ ni ihà ẹnu-ọ̀na ariwa; oju wọn si wà li ọ̀na gusu: ọkan ni iha ẹnu-ọ̀na ila-õrun, oju eyiti mbẹ li ọ̀na ariwa. 45 O si wi fun mi pe, Yàrá yi, ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na gusu, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ ile na. 46 Yará ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na ariwa, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ pẹpẹ na; awọn wọnyi li awọn ọmọ Sadoku ninu awọn ọmọ Lefi, ti nwọn ima sunmọ Oluwa lati ṣe iranṣẹ fun u. 47 O si wọ̀n agbalá na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn, ọgọrun igbọnwọ ni ibú, igun mẹrin lọgbọgba; ati pẹpẹ ti mbẹ niwaju ile na. 48 O si mu mi wá si iloro ile na, o si wọ̀n opo iloro na, igbọnwọ marun nihà ìhin, ati igbọnwọ marun nihà ọ̀hun: ibu ẹnu-ọ̀na na si jẹ igbọnwọ mẹta nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹta nihà ọ̀hun. 49 Gigùn iloro na jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ igbọnwọ mọkànla; o si mu mi wá si atẹ̀gun ti nwọn ifi ba gokè rẹ̀: ọwọ̀n pupọ̀ si mbẹ nihà ibi atẹrigbà, ọkan nihin, ati ọkan lọhun.

Esekieli 41

1 O si mu mi wá si tempili, o si wọ̀n awọn atẹrigbà, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakan, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakeji, ibú agọ na. 2 Ati ibú ilẹkùn na jẹ igbọnwọ mẹwa; ihà ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ marun li apakan, ati igbọnwọ marun li apakeji; o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogoji igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ. 3 O si wá si inu rẹ̀, o si wọ̀n atẹrigbà ilẹkùn na, igbọnwọ meji; ati ilẹkùn na, igbọnwọ mẹfa; ibú ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ meje. 4 Bẹ̃ li o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ, niwaju tempili: o si wi fun mi pe, Eyi ni ibi mimọ́ julọ. 5 O si wọ̀n ogiri ile na, igbọnwọ mẹfa; ati ibú yàrá-ihà gbogbo igbọnwọ mẹrin, yi ile na ka nihà gbogbo. 6 Ati awọn yará-ihà, ọkan lori ekeji jẹ mẹta, nigba ọgbọ̀n: nwọn si wọ̀ inu ogiri ti ile awọn yará-ihà na yika, ki nwọn ba le di ara wọn mu, nitori kò si idimú ninu ogiri ile na. 7 A si ṣe e gborò, o si lọ yika loke awọn yará ihà: nitori ogiri ile na lọ loke-loke yi ile na ka: nitorina ibú ile na wà loke, bẹ̃ni iyará isalẹ yọ si toke lãrin. 8 Emi si ri giga ile na yika: ipilẹ awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na si jẹ ije kikun kan ti igbọnwọ mẹfa ni gigun. 9 Ibú ogiri na, ti yará-ẹ̀gbẹ́ lode, jẹ igbọnwọ marun: ati eyi ti o kù ni ibi yará-ẹ̀gbẹ́ ti mbẹ ninu. 10 Ati lãrin yará na, ogún igbọnwọ ni gbigborò, yi ile na ka ni ihà gbogbo. 11 Ati ilẹkùn awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na mbẹ li ọ̀na ibi ti o kù, ilẹkùn kan li ọ̀na ariwa, ati ilẹkùn kan ni gusu: ati ibú ibẹ̀ na ti o kù, jẹ igbọnwọ marun yika. 12 Ati ile ti o wà niwaju eyiti a yà sọtọ̀ ni igun ọ̀na iwọ-õrun, jẹ ãdọrin igbọnwọ ni gbigborò; ogiri ile na si jẹ igbọnwọ marun ni ibú yika, ati gigùn rẹ̀, ãdọrun igbọnwọ. 13 O si wọ̀n ile na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn; ati ibi ti a yà sọtọ̀, ati ile na, pẹlu ogiri wọn, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn. 14 Ati ibú oju ile na, ati ti ibi ti a yà sọtọ̀ nihà ila-õrun ọgọrun igbọnwọ. 15 O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na; 16 Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na; 17 Si ti oke ilẹkun ani titi de ile ti inu, ati ti ode, ati lara ogiri niha gbogbo tinu tode ni wiwọ̀n. 18 Kerubu ati igi ọpẹ li a si fi ṣe e, igi ọpẹ kan si mbẹ lãrin kerubu ati kerubu: kerubu kọkan si ni oju meji; 19 Oju enia kan si wà nihà ibi igi ọpe li apa kan, ati oju ẹgbọ̀rọ kiniun kan si wà nihà ibi igi ọpẹ li apa keji: a ṣe e yi ile na ka niha gbogbo. 20 Lati ilẹ titi fi de okè ilẹkùn, ni a ṣe kerubu ati igi ọpẹ si, ati lara ogiri tempili na. 21 Awọn opó ilẹkùn tempili na jẹ igun mẹrin lọgbọgba: ati iwaju ibi mimọ́ irí ọkan bi irí ekeji. 22 Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa. 23 Ati tempili na, ati ibi mimọ́ na, ni ilẹkùn meji. 24 Awọn ilẹkùn mejeji na ni awẹ, awẹ meji ti nyi; awẹ meji fun ilẹkùn kan, ati awẹ meji fun ilẹkùn keji. 25 Kerubu, ati igi ọpẹ li a ṣe si ara wọn, sara ilẹkùn tempili, gẹgẹ bi eyiti a ṣe sara ogiri; igi ibori wà loju iloro lode. 26 Ferese toro ati igi ọpẹ mbẹ nihà ihin ati nihà ọhun nihà iloro, ati ni yará-iha ile na, ati ni igi ibori.

Esekieli 42

1 O si mu mi wá si agbala ode, li ọ̀na apa ariwa: o si mu mi wá si yará ti o kọju si ibi ti a yà sọtọ̀, ti o si kọju si ile lọna ariwa. 2 Niwaju, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn ni ilẹkun ariwa, ati ibú rẹ̀ ãdọta igbọnwọ. 3 Niwaju, ogún igbọnwọ ti o wà fun agbalá ti inu, ati niwaju itẹle ti o wà fun agbalá ti ode; ibujoko oke ti o kọju si ibujoko-oke wà ni orule mẹta. 4 Ati niwaju awọn yará ni irìn igbọnwọ mẹwa ni ibú ninu, ọ̀na igbọnwọ kan; ilẹkùn wọn si wà nihà ariwa. 5 Ati awọn yará oke kuru jù; nitori ibujoko ti awọn yará isalẹ ati yará ãrin yọ siwaju wọnyi ti ile. 6 Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá. 7 Ati ogiri ti o wà lode ti o kọju si yará, li apa agbala ode niwaju yará, gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ. 8 Nitori gigùn awọn yará ti o wà lode jẹ ãdọta igbọnwọ: si wò o, niwaju tempili o jẹ ọgọrun igbọnwọ. 9 Ati lati isalẹ yará wọnyi ni iwọle li ọ̀na ila-õrun wà, bi a ti nlọ sinu wọn lati agbala ode wá. 10 Ni ibú ogiri agbala, li ọ̀na ila-õrun niwaju ibiti a yà sọtọ̀, ati niwaju ile na, ni awọn yará na wà. 11 Ati ọ̀na iwaju wọn ti gẹgẹ bi iri awọn yará ti o wà li ọ̀na ariwa, bi nwọn ti gùn mọ, bẹ̃ ni nwọn gbòro mọ: ati gbogbo ijade wọn si dabi iṣe wọn, ati bi ilẹkùn wọn. 12 Bẹ̃ gẹgẹ ni yará ti on ti ilẹkùn wọn li ọ̀na gusu, ilẹkùn kan wà lori ọ̀na, li ọ̀na gbọran niwaju ogiri li ọ̀na ila-õrun bi a ti nwọ̀ inu wọn. 13 O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́. 14 Nigbati awọn alufa ba wọ̀ ibẹ̀, nwọn kì yio si kuro ni ibi mimọ́ si agbala ode, ṣugbọn nibẹ nibiti nwọn gbe nṣiṣẹ ni nwọn o fi ẹwù wọn si; nitori nwọn jẹ mimọ́; nwọn o si wọ̀ ẹwù miran, nwọn o si sunmọ nkan wọnni ti o jẹ́ ti enia. 15 Nigbati o si ti wọ̀n ile ti inu tan, o mu mi wá sihà ilẹkùn ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si wọ̀n yika. 16 O fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ila-õrun, ẹ̃dẹgbẹta ije, nipa ije iwọ̀nlẹ yika. 17 O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ariwa, ẹ̃dẹgbẹta ije yika. 18 O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa gusu, ẹ̃dẹgbẹta ije. 19 O yipadà si ọ̀na iwọ-õrun, o si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ọ, ẹ̃dẹgbẹta ije. 20 O wọ̀n ọ nihà mẹrẹrin: o ni ogiri kan yi i ka, ẹ̃dẹgbẹta ije ni gigùn, ati ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, lati pàla lãrin ibi mimọ́ ati ibi aimọ́.

Esekieli 43

1 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na, ẹnu-ọ̀na ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun: 2 Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wá lati ọ̀na ila-õrun: ati ohùn rẹ̀ ri bi ariwo omi pupọ̀: aiye si ràn fun ogo rẹ̀. 3 O si dabi irí iran ti mo ri, gẹgẹ bi iran ti mo ri nigbati mo wá lati pa ilu na run: iran na si dabi iran ti mo ri lẹba odò Kebari, mo si doju mi bolẹ. 4 Ogo Oluwa si wá si ile na lati ọ̀na ilẹkùn ti o kọjusi ọ̀na ila-õrun. 5 Ẹmi si gbe mi soke, o si mu mi wá si àgbala tinu: si kiye si i, ogo Oluwa kún ile na. 6 Mo si gbọ́ o mba mi sọ̀rọ lati inu ile wá; ọkunrin na si duro tì mi. 7 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn. 8 Ni titẹ́ iloro wọn nibi iloro mi, ati opó wọn nibi opó mi, ogiri si wà lãrin emi ati awọn, nwọn si ti ba orukọ mimọ́ mi jẹ nipa ohun irira wọn ti nwọn ti ṣe: mo si run wọn ni ibinu mi. 9 Njẹ ki nwọn mu panṣaga wọn, ati okú awọn ọba wọn jina kuro lọdọ mi, emi o si ma gbe ãrin wọn lailai. 10 Iwọ ọmọ enia, fi ile na hàn ile Israeli, ki oju aiṣedede wọn ba le tì wọn: si jẹ ki nwọn wọ̀n apẹrẹ na. 11 Bi oju gbogbo ohun ti nwọn ba ṣe ba si tì wọn, fi irí ile na hàn wọn, ati kikọ́ rẹ̀, ati ijade rẹ̀, ati iwọle rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo ofin rẹ̀; ki o si kọ ọ loju wọn, ki nwọn ki o lè pa gbogbo irí rẹ̀ mọ, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ki nwọn si ṣe wọn. 12 Eyi ni ofin ile na; Lori oke giga, gbogbo ipinnu rẹ̀ yika ni mimọ́ julọ. Kiyesi i, eyi ni ofin ile na. 13 Wọnyi si ni iwọ̀n pẹpẹ nipa igbọnwọ; Igbọnwọ jẹ igbọnwọ kan ati ibú atẹlẹwọ kan; isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ kan, ati igbati rẹ̀ ni eti rẹ̀ yika yio jẹ ika kan: eyi ni yio si jẹ ibi giga pẹpẹ na. 14 Lati isalẹ ilẹ titi de ijoko isalẹ yio jẹ igbọnwọ meji, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ́ kan; ati lati ijoko kekere titi de ijoko nla yio jẹ igbọnwọ mẹrin, ati ibú rẹ̀ igbọnwọ kan. 15 Pẹpẹ na si jẹ igbọnwọ mẹrin: ati lati pẹpẹ titi de oke jẹ iwo mẹrin. 16 Pẹpẹ na yio si jẹ igbọnwọ mejila ni gigùn, ati mejila ni ibú onigun mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀. 17 Ati ijoko ni yio jẹ igbọ̀nwọ mẹrinla ni gigun ati mẹrinla ni ibú ninu igun mẹrẹrin rẹ̀; ati eti rẹ̀ yika yio jẹ́ abọ̀ igbọnwọ; ati isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan yika; atẹgùn rẹ̀ yio si kọjusi iha ila-õrun. 18 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni aṣẹ pẹpẹ na li ọjọ ti nwọn o ṣe e, lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lori rẹ̀, ati lati wọ́n ẹ̀jẹ sori rẹ̀. 19 Iwọ o si fi ẹgbọrọ malu, fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, fun awọn alufa, awọn Lefi, ti iṣe iru-ọmọ Sadoku, ti nsunmọ mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, ni Oluwa Ọlọrun wi. 20 Iwọ o si mu ninu ẹjẹ rẹ̀, iwọ o si fi si iwo mẹrẹrin rẹ̀, ati si igun mẹrẹrin ijoko na, ati si eti rẹ̀ yika: iwọ o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọ́, iwọ o si ṣe etùtu rẹ̀. 21 Iwọ o si mu ẹgbọrọ malu ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, on o si sun u ni ibiti a yàn ni ile na lode ibi-mimọ́. 22 Ati ni ọjọ keji iwọ o fi ọmọ ewurẹ alailabawọn rubọ ọrẹ ẹ̀ṣẹ; nwọn o si sọ pẹpẹ na di mimọ́, bi nwọn iti ifi ẹgbọrọ malu sọ ọ di mimọ́. 23 Nigbati iwọ ba ti sọ ọ di mimọ tan, iwọ o fi ẹgbọrọ malu alailabawọn rubọ, ati àgbo alailabawọn lati inu agbo wá. 24 Iwọ o si fi wọn rubọ niwaju Oluwa, awọn alufa yio si dà iyọ̀ si wọn, nwọn o si fi wọn rú ọrẹ ẹbọ sisun si Oluwa. 25 Ọjọ meje ni iwọ o fi pèse obukọ fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ lojojumọ: nwọn o si pèse ẹgbọrọ malu pẹlu ati àgbo lati inu agbo wá, ti nwọn ṣe ailabawọn. 26 Ọjọ meje ni nwọn o fi wẹ̀ pẹpẹ, nwọn o si sọ ọ di mimọ́: nwọn o si yà ara wọn sọtọ̀. 27 Nigbati ọjọ wọnyi ba pe, yio si ṣe, ni ọjọ kẹjọ, ati siwaju, awọn alufa yio ṣe ọrẹ ẹbọ sisun nyin lori pẹpẹ, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ: emi o si gbà nyin, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 44

1 O si mu mi pada lọna ẹnu-ọ̀na ibi mimọ́ ti ode ti o kọju si ila-õrun; o si tì. 2 Oluwa si wi fun mi pe; Ẹnu-ọ̀na yi yio wà ni titì, a kì yio ṣi i, ẹnikan kì yio si gbà a wọ inu rẹ̀; nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti gbà a wọ inu rẹ̀, yio si wà ni titì. 3 Fun ọmọ-alade ni; ọmọ-alade, on ni yio joko ninu rẹ̀ lati jẹ akara niwaju Oluwa; yio wọ̀ ọ lati ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na na, yio si jade lati ọ̀na rẹ̀ na lọ. 4 O si mu mi wá ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa siwaju ile na; mo si wò, si kiyesi i, ogo Oluwa kun ile Oluwa: mo si doju mi bolẹ. 5 Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na. 6 Iwọ o si wi fun awọn ọlọ̀tẹ, ani fun ile Israeli, pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ki gbogbo ohun-irira nyin to fun nyin, ile Israeli, 7 Niti pe ẹ mu ọmọ-ajèji, alaikọla aiya, ati alaikọla ara wa, lati wà ni ibi-mimọ́ mi, lati sọ ọ di alailọ̀wọ, ani ile mi, nigbati ẹ rú akara mi, ọ̀ra ati ẹjẹ, nwọn si bà majẹmu mi jẹ nipa gbogbo ohun-irira nyin. 8 Ẹ kò si pa ibi-iṣọ́ ohun-mimọ́ mi mọ́: ṣugbọn ẹ ti yàn oluṣọ́ ibi-iṣọ́ inu ibi-mimọ́ mi fun ara nyin. 9 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Gbogbo ọmọ àjeji, alaikọla aiya, tabi alaikọla ara kì yio wọ̀ inu ibi mimọ́ mi, ninu gbogbo ọmọ àjeji ti o wà lãrin awọn ọmọ Israeli. 10 Ṣugbọn awọn Lefi ti o ti lọ jina kuro lọdọ mi, ni ìṣina Israeli, ti nwọn ṣìna kuro lọdọ mi lẹhin oriṣa wọn: yio si rù aiṣedede wọn. 11 Nwọn o si jẹ iranṣẹ ni ibi mimọ́ mi, oluṣọ́ ẹnu-ọ̀na ile, nwọn o si ma ṣe iranṣẹ ni ile: awọn ni yio pa ọrẹ-ẹbọ sisun ati ẹbọ fun awọn enia, nwọn o si duro niwaju wọn lati ṣe iranṣẹ fun wọn. 12 Nitori ti nwọn ṣe iranṣẹ fun wọn niwaju òriṣa wọn, nwọn si jẹ ohun ìdugbolu aiṣedede fun ile Israeli: nitorina ni mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi, nwọn o si rù aiṣedede wọn. 13 Nwọn kì yio si sunmọ ọdọ mi, lati ṣiṣẹ alufa fun mi, tabi lati sunmọ gbogbo ohun-mimọ́ mi, ni ibi mimọ́ julọ: nwọn o si rù itijú wọn, ati ohun-irira wọn ti nwọn ti ṣe. 14 Emi o si ṣe wọn ni oluṣọ́ ibi-iṣọ́ ile, fun gbogbo iṣẹ rẹ̀, ati fun ohun gbogbo ti a o ṣe ninu rẹ̀. 15 Ṣugbọn awọn alufa awọn Lefi, awọn ọmọ Sadoku, ti o pa ibi-iṣọ ibi mimọ́ mi mọ, nigbati awọn ọmọ Israeli ṣìna kuro lọdọ mi, awọn ni yio sunmọ ọdọ mi lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si duro niwaju mi lati rú ọrá ati ẹjẹ si mi, ni Oluwa Ọlọrun wi: 16 Awọn ni yio wá si ibi-mimọ́ mi, awọn ni o si sunmọ tabili mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si pa ibi-iṣọ́ mi mọ́. 17 Yio si ṣe pe, nigbati nwọn ba wá si ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, nwọn o wọ̀ ẹ̀wu ọ̀gbọ; irun agutan kì yio bọ́ si ara wọn, nigbati nwọn ba nṣe iranṣẹ ni ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, ati ninu ile. 18 Nwọn o si ni filà ọ̀gbọ li ori wọn, ṣòkoto ọ̀gbọ ni nwọn o si wọ̀ ni idí wọn; nwọn kì o si fi ohun ti imuni lãgùn dì amurè. 19 Nigbati nwọn ba si lọ si agbalá ode, ani si agbalá ode sọdọ awọn enia, nwọn o bọ́ ẹ̀wu wọn ti wọn ifi ṣe iranṣẹ, nwọn o si fi wọn si awọn yará mimọ́, nwọn o si wọ̀ ẹ̀wu miran; nwọn kì yio si fi ẹ̀wu wọn sọ awọn enia di mimọ́. 20 Nwọn kì o si fá ori wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio jẹ ki irun wọn gbọ̀; ni rirẹ nwọn o rẹ irun ori wọn. 21 Alufa gbogbo kì yio mu ọti-waini, nigbati nwọn ba wá si agbalá ti inu. 22 Nwọn kì yio si fẹ́ opo, tabi ẹniti a tì jade fun aya wọn: ṣugbọn nwọn o fẹ́ wundia lati iru-ọmọ ile Israeli, tabi opo ti o ti ni alufa ri. 23 Nwọn o si kọ́ awọn enia mi ni iyàtọ ti o wà lãrin mimọ́ ati ailọ̀wọ, nwọn o si mu wọn mọ̀ eyiti o wà lãrin aimọ́ ati mimọ́. 24 Ati ni ija, awọn ni yio duro lati ṣe idajọ; nwọn o si dá a ni idajọ mi: nwọn o si pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́ ni gbogbo apejọ mi; nwọn o si yà awọn ọjọ isimi mi si mimọ́. 25 Nwọn kì yio si wá sọdọ okú enia lati sọ ara wọn di aimọ́, ṣugbọn fun baba, tabi fun iya, tabi fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, fun arakunrin, tabi fun arabinrin ti kò ti ni ọkọ, nwọn le sọ ara wọn di aimọ́. 26 Ati lẹhin iwẹnumọ́ rẹ̀, nwọn o si ká ọjọ meje fun u. 27 Ati li ọjọ ti yio lọ si ibi-mimọ́, si agbalá ti inu, lati ṣe iranṣẹ ni ibi-mimọ́, on o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi. 28 Ati ogún ni yio jẹ fun wọn: emi ni ogún wọn: ẹ kì yio si fun wọn ni ini ni Israeli: emi ni ini wọn. 29 Awọn ni yio jẹ ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; ati gbogbo ohun-egún ni Israeli, yio jẹ́ ti wọn. 30 Ati ikini ninu gbogbo akọ́so nkan gbogbo, olukuluku ọrẹ gbogbo, ninu gbogbo ọrẹ nyin, yio jẹ ti awọn alufa: ẹ o si fi akọ́po iyẹfun nyin fun alufa, ki ibukun le bà le ile rẹ. 31 Gbogbo okú nkan, ati ohun ti a fà ya ninu ẹiyẹ tabi ninu ẹranko, ni awọn alufa kì yio jẹ.

Esekieli 45

1 PẸLUPẸLU nigbati ẹnyin ba fi ibo pín ilẹ li ogún, ẹ o gbé ọrẹ wá fun Oluwa, eyiti o mọ́ lati ilẹ na wá: gigùn na yio jẹ ẹgbã le ẹgbẹrun ije ni gigùn, ati ẹgbãrun ni ibú. Eyi yio jẹ́ mimọ́ ni gbogbo àgbegbe rẹ̀ yika. 2 Lati inu eyi, ẹ̃dẹgbẹta yio jẹ ti ibi-mimọ́ ni gigùn, pẹlu ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, ni igun mẹrẹrin yika; ati adọta igbọnwọ fun igbangba rẹ̀ yika. 3 Ati ninu ìwọn yi ni iwọ o wọ̀n ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbarun ni ibú; ati ninu rẹ̀ ni ibi-mimọ́ yio wà, ibi-mimọ́ julọ. 4 Eyi ti o mọ́ ninu ilẹ na yio jẹ ti awọn alufa, awọn iranṣẹ ibi-mimọ́, ti yio sunmọ lati ṣe iránṣẹ fun Oluwa: yio si jẹ àye fun ile wọn, ati ibi-mimọ́ fun ibi-mimọ́. 5 Ati ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigun, ati ti ẹgbãrun ni ibú, ni awọn Lefi, pẹlu awọn iranṣẹ ile na, ni ogún yará, fun ara wọn, ni ini. 6 Ati ini ilu na li ẹnyin o yàn ẹgbarun ni ibú, ati ẹgba mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, lẹba ọrẹ ipín mimọ́ na: yio jẹ ti gbogbo ile Israeli. 7 Ati ipín kan yio jẹ ti olori nihà kan ati niha keji ọrẹ ipin mimọ́, ati ti ini ilu, ti o kọju si ọrẹ ipín mimọ́, ti o si kọju si iní ti ilu, lati iha iwọ-õrun si iwọ-õrun, ati lati ihà ila-õrun si ila-õrun: gigùn rẹ̀ yio gbe ọkan ninu awọn ipín, lati eti iwọ-õrun de eti ila-õrun. 8 Ni ilẹ na ni iní rẹ̀ yio wà ni Israeli: awọn olori mi kì yio si ni awọn enia mi lara mọ́; ati ilẹ iyokù ni nwọn o fi fun ile Israeli gẹgẹ bi ẹyà wọn. 9 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi. 10 Ki ẹnyin ki o ni ìwọn títọ, ati efà títọ, ati bati títọ. 11 Efa ati bati yio jẹ ìwọn kanna, ki bati ba le gbà ìdamẹwa homeri, ati efa idamẹwa homeri: iwọ̀n rẹ̀ yio jẹ gẹgẹ bi ti homeri. 12 Ṣekeli yio si jẹ́ ogún gera: ogún ṣekeli, ṣekeli mẹdọgbọ̀n, ṣekeli mẹdogun, ni manẹ nyin yio jẹ. 13 Eyi ni ọrẹ ti ẹ o rú; idamẹfa efa homeri alikama kan, ẹ o si mu idamẹfa efa homeri barle kan wá. 14 Niti aṣẹ oróro, bati oróro, idamẹwa bati kan, lati inu kori wá, ti o jẹ homeri onibati mẹwa; nitori bati mẹwa ni homeri kan: 15 Ati ọdọ-agutan kan lati inu agbo, lati inu igba, lati inu pápa tutù Israeli; fun ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati fun ọrẹ ẹbọ sisun, fun ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati fi ṣe ètutu fun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi. 16 Gbogbo enia ilẹ na ni yio mu ẹbọ yi wá fun olori ni Israeli. 17 Ti ọmọ-alade yio jẹ́ ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ mimu, ninu asè gbogbo, ati ni oṣù titun, ati ni awọn ọjọ isimi, ni gbogbo ajọ ile Israeli: on o pèse ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati ṣe etùtu fun ile Israeli. 18 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; li oṣù ekini, li ọjọ ekini oṣù, iwọ o mu ẹgbọ̀rọ akọ malu alailabawọn, iwọ o si fi sọ ibi mimọ́ di mimọ́: 19 Alufa yio si mu ninu ẹjẹ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, yio si fi si opó ile, ati si igun mẹrẹrin ijoko pẹpẹ, ati si opó ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu ile. 20 Bayi ni iwọ o si ṣe li ọjọ keje oṣù fun olukuluku ẹniti o ṣina, ati fun òpe: ẹ o si ṣe etùtu ilẹ na. 21 Li oṣù ekini, li ọjọ ẹkẹrinla oṣù, ẹnyin o ni irekọja, asè ọjọ meje: akara aiwú ni jijẹ. 22 Ati li ọjọ na ni ọmọ-alade yio pèse ẹgbọ̀rọ akọ malu fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ara rẹ̀ ati fun gbogbo enia ilẹ na. 23 Ati ọjọ meje àse na ni yio pèse ọrẹ ẹbọ sisun fun Oluwa, ẹgbọ̀rọ akọ malu meje ati àgbo meje alailabawọ́n lojojumọ fun ọjọ meje na; ati ọmọ ewurẹ kan lojojumọ fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 24 Yio si pèse ọrẹ ẹbọ jijẹ ti efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun àgbo kan, ati hini ororo kan fun efa kan. 25 Li oṣù keje, li ọjọ kẹ̃dogun oṣù, ni yio ṣe gẹgẹ bi wọnyi ni àse ọjọ meje, gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ sisun, ati gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati gẹgẹ bi oróro.

Esekieli 46

1 BAYI li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹnu-ọ̀na agbala ti inu ti o kọju si ila-õrun yio wà ni titì ni ọjọ mẹfa ti a fi iṣiṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ isimi li a o ṣi i silẹ, ati li ọjọ oṣù titun li a o si ṣi i silẹ. 2 Olori na yio si ba ẹnu-ọ̀na iloro ti ẹnu-ọ̀na ode wọle, yio si duro nibi opó ẹnu-ọ̀na, awọn alufa yio si pèse ọrẹ ẹbọ sisun rẹ̀ ati ọrẹ ẹbọ idupẹ rẹ̀, on o si ma sìn ni iloro ẹnu-ọ̀na: yio si jade wá; a kì yio si tì ẹnu-ọ̀na titi di aṣalẹ. 3 Enia ilẹ na yio si ma sìn ni ilẹkùn ẹnu-ọ̀na yi niwaju Oluwa ni ọjọ isimi, ati ni oṣù titun. 4 Ọrẹ-ẹbọ sisun ti olori na yio rú si Oluwa ni ọjọ isimi, yio jẹ ọdọ-agutan mẹfa alailabawọn, ati agbò kan alailabàwọn. 5 Ati ọrẹ ẹbọ jijẹ yio jẹ efà kan fun agbò kan, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan. 6 Ati li ọjọ oṣù titun, ẹgbọ̀rọ malũ kan ailabawọn, ati ọdọ-agutan mẹfa, ati agbò kan: nwọn o wà lailabàwọn. 7 Yio si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ, efa fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan gẹgẹ bi ọwọ́ rẹ̀ ba ti to, ati hini ororo kan fun efa kan. 8 Nigbati olori na yio ba si wọle, ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na ni yio ba wọle, yio si ba ọ̀na rẹ̀ jade. 9 Nigbati enia ilẹ na yio ba si wá siwaju Oluwa ni awọn apejọ ọ̀wọ, ẹniti o ba ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa wọle lati sìn, yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu jade; ẹniti o ba si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu wọle yio si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa jade; kì yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ti o ba wọle jade, ṣugbọn yio jade lodi keji. 10 Ati olori ti o wà lãrin wọn, nigbati nwọn ba wọle, yio wọle; nigbati nwọn ba si jade, yio jade. 11 Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan. 12 Nigbati olori na yio ba si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun atinuwá, tabi ọrẹ-ẹbọ idupẹ atinuwá fun Oluwa, ẹnikan yio si ṣi ilẹkun ti o kọjusi ila-õrun fun u, yio si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ idupẹ rẹ̀, bi o ti ṣe li ọjọ-isimi: yio si jade; ati lẹhin ijadelọ rẹ̀ ẹnikan yio tì ilẹkun. 13 Li ojojumọ ni iwọ o pèse ọdọ agutan kan alailabawọn ọlọdun kan fun ọrẹ-ẹbọ sisun fun Oluwa: iwọ o ma pèse rẹ̀ lorowurọ̀. 14 Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa. 15 Bayi ni nwọn o pèse ọdọ-agutan na, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ na, ati ororo na, lojojumọ fun ọrẹ-ẹbọ sisun nigbagbogbo. 16 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun. 17 Bi o ba si fi ẹbùn ninu ini rẹ̀ fun ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, nigbana yio jẹ tirẹ̀ titi di ọdun omnira; yio si tun pada di ti olori na: ṣugbọn ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀ fun wọn. 18 Olori na kì yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rẹ̀ lara ini ti ontikalarẹ̀: ki awọn enia mi ki o má ba tuká, olukuluku kuro ni ini rẹ̀. 19 O si mu mi kọja li abawọ̀, ti o wà lẹba ẹnu-ọ̀na, si awọn yará mimọ́ ti awọn alufa, ti o kọjusi ariwa: si kiyesi i, ibi kan wà nibẹ̀ ni ihà mejeji iwọ-õrun. 20 O si wi fun mi pe, Eyi ni ibiti awọn alufa yio ma sè ọrẹ irekọja ati ọrẹ ẹ̀ṣẹ, nibiti nwọn o ma yan ọrẹ jijẹ; ki nwọn má ba gbe wọn jade si agbalá ode, lati sọ awọn enia di mimọ́. 21 O si mu mi jade wá si agbalá ode, o si mu mi kọja ni igun mẹrẹrin agbalá na; si kiyesi i, ni olukuluku igun agbalá na ni agbala kan gbe wà. 22 Ni igun mẹrẹrin agbalá na, ni agbalá ti a kànpọ ologoji igbọnwọ ni gigùn, ati ọgbọ̀n ni ibú: awọn igun mẹrẹrin wọnyi jẹ iwọ̀n kanna. 23 Ọwọ́ ile kan si wà yika ninu wọn, yika awọn mẹrẹrin, a si ṣe ibudaná si abẹ ọwọ́ na yika. 24 O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ibi awọn ti nsè, nibiti awọn iranṣẹ ile na yio ma se ẹbọ awọn enia.

Esekieli 47

1 O si mu mi padà wá si ibi ilẹkùn ile na; si kiyesi i, omi ntù jade lati abẹ iloro ile na nihà ila-õrun: nitori iwaju ile na wà ni ila-õrun, omi si nwalẹ lati abẹ apa ọtun ile na, ni gusu pẹpẹ. 2 O si mu mi jade ni ọ̀na ẹnu-ọ̀na ihà ariwa, o si mu mi yi wá ọ̀na ode si ẹnu-ọ̀na ode ni ọ̀na ti o kọjusi ila-õrun; si kiyesi i, omi ṣàn jade lati ihà ọtun. 3 Nigbati ọkunrin na jade sihà ila-õrun, pẹlu okùn kan lọwọ rẹ̀, o si wọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ, o si mu mi là omi na ja; omi na si de kókosẹ̀. 4 O tun wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là omi na ja; omi na si de ẽkun. O si wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là a ja; omi si de ẹgbẹ́. 5 O si wọ̀n ẹgbẹrun; odò ti nkò le wọ́: nitori omi ti kún, omi ilúwẹ, odò ti kò ṣe rekọja. 6 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Iwọ ri yi? O si mu mi wá, o si mu mi pada wá si bèbe odò na. 7 Nigbati mo pada, si kiyesi i, igi pupọ̀pupọ̀ wà ni ihà ihin ati ni ihà ọhun li eti odò na. 8 O si wi fun mi pe, Omi wọnyi ntú jade sihà ilẹ ila-õrun, nwọn si nsọkalẹ lọ si pẹ̀tẹlẹ, nwọn si wọ̀ okun lọ: nigbati a si mu wọn wọ̀ inu okun, a si mu omi wọn lara dá. 9 Yio si ṣe pe, ohunkohun ti o ba wà lãye ti nrakò, nibikibi ti odò mejeji ba de, yio wà lãye: ọ̀pọlọpọ ẹja yio si de, nitori omi wọnyi yio de ibẹ̀: a o si mu wọn lara dá; ohun gbogbo yio si yè nibikibi ti odò na ba de. 10 Yio si ṣe pe, Awọn apẹja yio duro lori rẹ̀ lati Engedi titi de Eneglaimu; nwọn o jẹ ibi lati nà àwọn si; ẹja wọn o dabi iru wọn, bi ẹja okun-nla, lọpọlọpọ. 11 Ṣugbọn ibi ẹrẹ̀ rẹ̀ ati ibi irà rẹ̀ li a kì o mu laradá; a o fi nwọn fun iyọ̀. 12 Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá. 13 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji. 14 Ẹnyin o si jogún rẹ̀, olukuluku bi ti ekeji rẹ̀: eyiti mo ti gbe ọwọ́ mi sokè lati fi i fun awọn baba nyin: ilẹ yi yio si bọ sọdọ nyin fun ogún. 15 Eyi ni yio si jẹ ãlà ilẹ na nihà ariwa, lati okun nla, ni ọ̀na Hetloni, bi a ti nlọ si Sedadi; 16 Hamati, Berota, Sibraimu, ti o wà lãrin ãlà Damasku, ati ãlà Hamati; Hasar-hatikonu, ti o wà ni agbègbe Haurani. 17 Alà lati okun yio si jẹ Hasarenani, ãlà Damasku, ati ariwa nihà ariwa, ati ãlà Hamati. Eyi si ni ihà ariwa. 18 Ati ni ihà ila-õrun ẹ o wọ̀n lati ãrin Haurani, ati lati ãrin Damasku, ati lati ãrin Gileadi, ati lati ãrin ilẹ Israeli lẹba Jordani, lati ãlà titi de okun ila-õrun. Eyi ni ihà ila-õrun. 19 Ati ihà gusu si gusu, lati Tamari titi de omi ijà ni Kadeṣi, pẹ̀tẹlẹ si okun nla. Eyi ni ihà gusu. 20 Ihà iwọ-õrun pẹlu yio jẹ okun nla lati ãlà bi a ti nlọ si Hamati. Eyi ni ihà iwọ-õrun. 21 Bayi li ẹ o pin ilẹ yi fun ara nyin gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya Israeli. 22 Yio si ṣe pe, ìbo ni ẹ o fi pin i ni ogún fun ara nyin, ati fun awọn alejo ti o ṣe atipo lãrin nyin, ti nwọn bi ọmọ lãrin nyin: nwọn o si ri si nyin bi ibilẹ ninu awọn ọmọ Israeli; nwọn o ba nyin pin i li ogún lãrin awọn ẹ̀ya Israeli. 23 Yio si ṣe pe, ni ẹ̀ya ti alejò ba ṣe atipo, nibẹ̀ li ẹ o fun u ni ogún, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esekieli 48

1 WỌNYI si ni orukọ awọn ẹ̀ya na. Lati opin ariwa titi de ọwọ́ ọ̀na Hetlonu, bi a ba nlọ si Hamati, Hasaenani, leti Damasku niha ariwa, de ọwọ́ Hamati; wọnyi sa ni ihà rẹ̀ ni ila-õrun ati iwọ-õrun; ipin kan fun Dani. 2 Ati ni àgbegbe Dani, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Aṣeri. 3 Ati ni àgbegbe Aṣeri, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Naftali. 4 Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse. 5 Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu. 6 Ati ni àgbegbe Efraimu, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Reubeni. 7 Ati ni àgbegbe Reubeni, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Juda. 8 Ati ni àgbegbe Juda, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun ni yio jẹ ọrẹ ti ẹnyin o ta, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ije ni ibú, ati ni gigùn, bi ọkan ninu awọn ipin iyokù, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀. 9 Ọrẹ ti ẹnyin o si ta fun Oluwa yio jẹ ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú. 10 Ati fun wọn, ani fun awọn alufa, ni ọrẹ mimọ́ yi yio jẹ; ni ihà ariwa, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà gusu, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀. 11 Yio jẹ ti awọn alufa ti a yà si mimọ́, ninu awọn ọmọ Sadoku; ti nwọn ti pa ilàna mi mọ, ti nwọn kò si ṣìna ni iṣìna awọn ọmọ Israeli, bi awọn Lefi ti ṣìna. 12 Ọrẹ ilẹ ti a si ta yi, yio jẹ ohun mimọ́ julọ fun wọn li àgbegbe awọn Lefi. 13 Ati ni ikọjusi àgbegbe awọn alufa, ni awọn Lefi yio ni ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú: gigùn gbogbo rẹ̀ yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ati ibú rẹ̀, ẹgbã-marun. 14 Nwọn kì yio si tà ninu rẹ̀, nwọn kì yio si fi ṣe paṣiparọ, bẹ̃ni nwọn kì yio si fi akọ́so ilẹ na si ọwọ́ ẹlomiran, nitoripe o jẹ mimọ́ fun Oluwa. 15 Ati ẹgbẹ̃dọgbọn ti o kù ni ibú, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun na, yio jẹ ibi aimọ́ fun ilu-nla na, fun ibugbe, ati fun àgbegbe: ilu-nla na yio si wà lãrin rẹ̀. 16 Wọnyi ni yio si jẹ iwọ̀n rẹ̀; ni ihà ariwa, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta. 17 Awọn àgbegbe ilu-nla na yio jẹ niha ariwa, ãdọtalerugba, ati nihà gusu, ãdọtalerugba ati nihà ila-õrun, ãdọtalerugba, ati nihà iwọ-õrun, ãdọtalerugba. 18 Ati iyokù ni gigùn, ni ikọjusi ọrẹ ti ipin mimọ́ na, yio si jẹ ẹgbã-marun nihà ila-õrun, ati ẹgbã-marun nihà iwọ-õrun: yio si wà ni ikọjusi ọrẹ ipin mimọ́ na, ati ibisi rẹ̀ yio jẹ fun onjẹ fun awọn ti nsìn ni ilu-nla na. 19 Awọn ti mba nsìn ilu-nla na yio si ma sìn i, lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli. 20 Gbogbo ọrẹ na yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, nipa ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun: ẹ o si ta ọrẹ mimọ́ na, igun mẹrẹrin lọgbọ̃gba pẹlu ini ilu-nla na. 21 Ati iyokù yio jẹ ti olori, ni ihà kan, ati nihà keji ti ọrẹ mimọ́ na, ati ti ini ibi nla na, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ọrẹ ti àgbegbe ila-õrun, ati nihà iwọ-õrun ni ikọjusi ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun, nihà àgbegbe iwọ-õrun, ni ikọjusi awọn ipin ti olori: yio si jẹ ọrẹ mimọ́ na; ibi mimọ́ ile na, yio si wà lãrin rẹ̀. 22 Ati lati ini awọn Lefi, ati lati ini ti ilu-nla na, lãrin eyiti iṣe ti olori, lãrin àgbegbe Juda, ati lãrin àgbegbe Benjamini, yio jẹ ti olori. 23 Ati fun awọn ẹ̀ya iyokù, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Benjamini ipin kan. 24 Ati ni àgbegbe Benjamini, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Simeoni ipin kan. 25 Ati ni àgbegbe Simeoni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Issakari ipin kan. 26 Ati ni àgbegbe Issakari, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Sebuloni ipin kan. 27 Ati ni àgbegbe Sebuloni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Gadi ipin kan. 28 Ati ni àgbegbe Gadi, ni ihà gusu si gusu, àgbegbe na yio jẹ lati Tamari de omi ijà ni Kadeṣi, ati si odò, titi de okun nla. 29 Eyi ni ilẹ ti ẹnyin o fi ìbo pin ni ogún fun awọn ẹ̀ya Israeli, wọnyi si ni ipin wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi. 30 Wọnyi si ni ibajade ti ilu-nla na lati ìha ariwa, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta oṣùwọn. 31 Awọn bode ilu-nla na yio jẹ gẹgẹ bi orukọ awọn ẹ̀ya Israeli: bodè mẹta nihà ariwa, bodè Reubeni ọkan, bodè Juda ọkan, bodè Lefi ọkan. 32 Ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta: ati bodè mẹta; ati bode Josefu ọkan, bode Benjamini ọkan, bodè Dani ọkan. 33 Ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta ìwọn: ati bodè mẹta; bodè Simeoni ọkan, bodè Issakari ọkan, bodè Sebuloni ọkan. 34 Ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, pẹlu bodè mẹta wọn; bodè Gadi ọkan, bodè Aṣeri ọkan, bodè Naftali ọkan. 35 O jẹ ẹgbã-mẹsan ìwọn yika: orukọ ilu-nla na lati ijọ na lọ yio ma jẹ, Oluwa mbẹ nibẹ̀.

Danieli 1

Àwọn Ọdọmọkunrin kan ní Ààfin Nebukadnessari

1 LI ọdun kẹta ijọba Jehoiakimu, ọba Juda ni Nebukadnessari, ọba Babeli, wá si Jerusalemu, o si do tì i. 2 Oluwa si fi Jehoiakimu, ọba Juda le e lọwọ, pẹlu apakan ohun-elo ile Ọlọrun, ti o kó lọ si ilẹ Ṣinari, si ile oriṣa rẹ̀: o si kó ohun-elo na wá sinu ile-iṣura oriṣa rẹ̀. 3 Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye; 4 Awọn ọmọ ti kò lẹgan lara, ṣugbọn awọn ti o ṣe arẹwa, ti o si ni ìmọ ninu ọgbọ́n gbogbo, ti o mọ̀ oye, ti o si ni iyè ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro li ãfin ọba ati awọn ti a ba ma kọ́ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea. 5 Ọba si pese onjẹ wọn ojojumọ ninu adidùn ọba ati ninu ọti-waini ti o nmu: ki a bọ wọn bẹ̃ li ọdun mẹta, pe, li opin rẹ̀, ki nwọn ki o le duro niwaju ọba. 6 Njẹ ninu awọn wọnyi ni Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, lati inu awọn ọmọ Juda: 7 Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego. 8 Ṣugbọn Danieli pinnu rẹ̀ li ọkàn rẹ̀ pe, on kì yio fi onjẹ adidùn ọba, ati ọti-waini ti o nmu ba ara on jẹ: nitorina o bẹ̀ olori awọn iwẹfa pe, ki on má ba ba ara on jẹ. 9 Ọlọrun sa ti mu Danieli ba ojurere ati iyọ́nu pade lọdọ olori awọn iwẹfa. 10 Olori awọn iwẹfa si wi fun Danieli pe, Mo bẹ̀ru ọba, oluwa mi, ẹniti o yàn onjẹ nyin ati ohun mimu nyin: nitori bawo li on o ṣe ri oju nyin ki o faro jù ti awọn ọmọkunrin ẹgbẹ nyin kanna lọ? nigbana li ẹnyin o ṣe ki emi ki o fi ori mi wewu lọdọ ọba. 11 Nigbana ni Danieli wi fun olutọju ti olori awọn iwẹfa fi ṣe oluṣọ Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah pe, 12 Dán awọn ọmọ-ọdọ rẹ wò, emi bẹ̀ ọ, ni ijọ mẹwa; ki o si jẹ ki nwọn ki o ma fi ẹ̀wa fun wa lati jẹ, ati omi lati mu. 13 Nigbana ni ki a wò oju wa niwaju rẹ, ati oju awọn ọmọ ti njẹ onjẹ adidùn ọba: bi iwọ ba si ti ri i si, bẹ̃ni ki o ṣe si awọn ọmọ-ọdọ rẹ. 14 Bẹ̃li o gbà fun wọn li ọ̀ran yi, o si dan wọn wò ni ijọ mẹwa. 15 Li opin ọjọ mẹwa, a ri oju wọn lẹwa, nwọn si sanra jù gbogbo awọn ti njẹ onjẹ adidùn ọba lọ. 16 Bẹ̃ni olutọju mu onjẹ adidùn wọn kuro, ati ọti-waini ti nwọn iba mu, o si fun wọn li ẹ̀wa. 17 Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ ati oye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli si li oye ni gbogbo iran ati alá. 18 Nigbati o si di opin ọjọ ti ọba ti da pe ki a mu wọn wá, nigbana ni olori awọn iwẹfa mu wọn wá siwaju Nebukadnessari. 19 Ọba si ba wọn sọ̀rọ: ninu gbogbo wọn, kò si si ẹniti o dabi Danieli, Hananiah, Miṣaeli ati Asariah: nitorina ni nwọn fi nduro niwaju ọba. 20 Ati ninu gbogbo ọ̀ran ọgbọ́n ati oye, ti ọba mbère lọwọ wọn, o ri pe ni iwọn igba mẹwa, nwọn sàn jù gbogbo awọn amoye ati ọlọgbọ́n ti o wà ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀ lọ. 21 Danieli si wà sibẹ titi di ọdun ikini ti Kirusi, ọba.

Danieli 2

Àlá Nebukadnessari

1 ATI li ọdun keji ijọba Nebukadnessari, Nebukadnessari lá alá nipa eyi ti ọkàn rẹ̀ kò fi le ilẹ ninu rẹ̀, ti orun si dá loju rẹ̀. 2 Nigbana ni ọba paṣẹ pe, ki a pè awọn amoye ati ọlọgbọ́n, ati awọn oṣó, ati awọn Kaldea wá, lati fi alá ọba na hàn fun u. Bẹ̃ni nwọn si duro niwaju ọba. 3 Ọba si wi fun wọn pe, mo lá alá kan, ọkàn mi kò si le ilẹ lati mọ̀ alá na. 4 Nigbana ni awọn Kaldea wi fun ọba li ede awọn ara Siria pe, Ki ọba ki o pẹ́: rọ́ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ, awa o si fi itumọ̀ na hàn. 5 Ọba dahùn o si wi fun awọn Kaldea pe, ohun na ti kuro li ori mi: bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, a o ké nyin wẹwẹ, a o si sọ ile nyin di ãtàn. 6 Ṣugbọn bi ẹnyin ba fi alá na hàn, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, ẹnyin o gba ẹ̀bun ati ọrẹ ati ọlá nla li ọwọ mi: nitorina, ẹ fi alá na hàn fun mi, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu. 7 Nwọn tun dahùn nwọn si wipe, Ki ọba ki o rọ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, awa o si fi itumọ̀ rẹ̀ hàn. 8 Ọba si dahùn o wi pe, emi mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin fẹ mu akoko pẹ, nitoriti ẹnyin ri pe nkan na lọ li ori mi. 9 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi, njẹ ipinnu kan li ẹnyin ti ṣe: nitoriti ẹnyin mura lati ma sọ̀rọ eke ati idibajẹ niwaju mi, titi akoko yio fi kọja: nitorina ẹ rọ́ alá na fun mi emi o si mọ̀ pe ẹnyin o le fi itumọ̀ rẹ̀ hàn fun mi pẹlu. 10 Awọn Kaldea si dahùn niwaju ọba, nwọn si wipe, kò si ẹnikan ti o wà li aiye ti o le fi ọ̀ran ọba hàn: kò si si ọba, oluwa, tabi ijoye kan ti o bère iru nkan bẹ̃ lọwọ amoye, tabi ọlọgbọ́n, tabi Kaldea kan ri. 11 Ohun ti o tilẹ ṣọwọ́n ni ọba bère, kò si si ẹlomiran ti o le fi i hàn niwaju ọba bikoṣe awọn oriṣa, ibugbe ẹniti kì iṣe ninu ẹran-ara. 12 Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run. 13 Nigbana ni aṣẹ jade lọ pe, ki nwọn ki o pa awọn amoye; nwọn si nwá Danieli pẹlu awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lati pa wọn.

Ọlọrun fi Àlá Ọba ati Ìtumọ̀ Rẹ̀ Han Daniẹli

14 Nigbana ni Danieli fi ìmọ ati ọgbọ́n dahùn wi fun Arioku, ti iṣe balogun ẹṣọ ọba, ẹniti nlọ pa awọn amoye Babeli. 15 O dahùn o si wi fun Arioku, balogun ọba pe, Ẽṣe ti aṣẹ fi yá kánkán lati ọdọ ọba wá bẹ̃? Nigbana ni Arioku fi nkan na hàn fun Danieli. 16 Nigbana ni Danieli wọle lọ, o si bère lọwọ ọba pe, ki o fi akokò fun on, o si wipe, on o fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba. 17 Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀. 18 Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli. 19 Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun. 20 Danieli dahùn o si wipe, Olubukún ni orukọ Ọlọrun titi lai; nitori tirẹ̀ li ọgbọ́n ati agbara. 21 O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye: 22 O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà. 23 Mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si fi iyìn fun ọ, iwọ Ọlọrun awọn baba mi, ẹniti o fi ọgbọ́n ati agbara fun mi, ti o si fi ohun ti awa bère lọwọ rẹ hàn fun mi nisisiyi: nitoriti iwọ fi ọ̀ran ọba hàn fun wa nisisiyi.

Daniẹli Rọ́ Àlá Ọba, Ó sì Sọ Ìtumọ̀ Rẹ̀

24 Nigbana ni Danieli wọle tọ Arioku lọ, ẹniti ọba yàn lati pa awọn ọlọgbọ́n Babeli run, o si lọ, o si wi fun u bayi pe; Máṣe pa awọn ọlọgbọ́n Babeli run: mu mi lọ siwaju ọba, emi o si fi itumọ na hàn fun ọba. 25 Nigbana li Arioku yara mu Danieli lọ siwaju ọba, o si wi bayi fun u pe, Mo ri ọkunrin kan ninu awọn ọmọ igbekun Juda, ẹniti yio fi itumọ na hàn fun ọba. 26 Ọba dahùn o si wi fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari pe, Iwọ le fi alá ti mo la hàn fun mi, ati itumọ rẹ̀ pẹlu? 27 Danieli si dahùn niwaju ọba, o si wipe, Aṣiri ti ọba mbère, awọn ọlọgbọ́n, awọn oṣó, awọn amoye, ati awọn alafọṣẹ, kò le fi hàn fun ọba. 28 Ṣugbọn Ọlọrun kan mbẹ li ọrun ti o nfi aṣiri hàn, ẹniti o si fi hàn fun Nebukadnessari ohun ti mbọ wá ṣe ni ikẹhin ọjọ. Alá rẹ, ati iran ori rẹ lori akete rẹ, ni wọnyi; 29 Ọba, iwọ nronu lori akete rẹ, ohun ti yio ṣe lẹhin ọla, ati ẹniti o nfi aṣiri hàn funni mu ọ mọ̀ ohun ti mbọ wá ṣe. 30 Ṣugbọn bi o ṣe temi ni, a kò fi aṣiri yi hàn fun mi nitori ọgbọ́n ti emi ni jù ẹni alãye kan lọ, ṣugbọn nitori ki a le fi itumọ na hàn fun ọba, ati ki iwọ ki o le mọ̀ èro ọkàn rẹ. 31 Iwọ ọba nwò, si kiyesi, ere nla kan. Ere giga yi, ti didan rẹ̀ pọ̀ gidigidi, o duro niwaju rẹ, ìrí rẹ̀ si ba ni lẹ̀ru gidigidi. 32 Eyi ni ere na; ori rẹ̀ jẹ wura daradara, aiya ati apa rẹ̀ jẹ fadaka, inu ati ẹ̀gbẹ rẹ̀ jẹ idẹ, 33 Itan rẹ̀ jẹ irin, ẹsẹ rẹ̀ si jẹ apakan irin, apakan amọ̀. 34 Iwọ ri titi okuta kan fi wá laisi ọwọ, o si kọlu ere na lẹsẹ rẹ̀, ti iṣe ti irin ati amọ̀, o si fọ́ wọn tũtu. 35 Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye. 36 Eyiyi li alá na; awa o si sọ itumọ rẹ̀ pẹlu niwaju ọba. 37 Iwọ ọba, li ọba awọn ọba: nitori Ọlọrun ọrun ti fi ijọba, agbara, ati ipá, ati ogo fun ọ. 38 Ati nibikibi ti ọmọ enia wà, ẹranko igbẹ ati ẹiyẹ oju-ọrun li o si fi le ọ lọwọ, o si ti fi ọ ṣe alakoso lori gbogbo wọn. Iwọ li ori wura yi. 39 Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye. 40 Ijọba kẹrin yio si le bi irin; gẹgẹ bi irin ti ifọ tũtu, ti si iṣẹgun ohun gbogbo: ati gẹgẹ bi irin na ti o fọ gbogbo wọnyi, bẹ̃ni yio si fọ tũtu ti yio si lọ̀ wọn kunna. 41 Ati gẹgẹ bi iwọ ti ri ẹsẹ ati ọmọkasẹ ti o jẹ apakan amọ̀ amọkoko, ati apakan irin, ni ijọba na yio yà si ara rẹ̀; ṣugbọn ipá ti irin yio wà ninu rẹ̀, niwọn bi iwọ ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀. 42 Gẹgẹ bi ọmọkasẹ na ti jẹ apakan irin ati apakan amọ̀, bẹ̃li apakan ijọba na yio lagbara, apakan yio si jẹ ohun fifọ. 43 Ati gẹgẹ bi iwọ si ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀, nwọn o da ara wọn pọ mọ iru-ọmọ enia, ṣugbọn nwọn kì yio fi ara wọn mọ ara wọn, gẹgẹ bi irin kì ti idapọ mọ amọ̀. 44 Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai. 45 Gẹgẹ bi iwọ si ti ri ti okuta na wá laisi ọwọ lati òke wá, ti o si fọ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wura wọnni tutu; Ọlọrun titobi ti fi hàn fun ọba, ohun ti mbọ wá ṣe lẹhin ọla: otitọ si li alá na, itumọ rẹ̀ si daju.

Ọba fún Daniẹli ní Ẹ̀bùn

46 Nigbana ni Nebukadnessari, ọba, wolẹ o si doju rẹ̀ bolẹ, o si fi ori balẹ fun Danieli, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o ṣe ẹbọ-ọrẹ ati õrùn didùn fun u. 47 Ọba da Danieli lohùn, o si wipe, Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba, ati olufihàn gbogbo aṣiri, nitori ti iwọ le fi aṣiri yi hàn. 48 Nigbana li ọba sọ Danieli di ẹni-nla, o si fun u li ẹ̀bun nla pupọ, o si fi i jẹ olori gbogbo igberiko Babeli, ati olori onitọju gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli. 49 Danieli si bère lọwọ ọba, o si fi Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego jẹ olori ọ̀ran igberiko Babeli; ṣugbọn Danieli joko li ẹnu-ọ̀na ãfin ọba.

Danieli 3

Nebukadinessari Pàṣẹ pé kí Gbogbo Eniyan máa Sin Ère Wúrà tí ó gbé kalẹ̀

1 NEBUKADNESSARI ọba, si yá ere wura kan, eyi ti giga rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa: o si gbé e kalẹ ni pẹtẹlẹ Dura, ni igberiko Babeli. 2 Nigbana ni Nebukadnessari ọba, ranṣẹ lọ ipè awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, ati awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko, lati wá si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari ọba, gbé kalẹ. 3 Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ. 4 Nigbana ni akede kigbe soke pe, A pa a laṣẹ fun nyin, ẹnyin enia, orilẹ, ati ède gbogbo, 5 Pe, akokò ki akokò ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki ẹnyin wolẹ, ki ẹ si tẹriba fun ere wura ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ. 6 Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo. 7 Nitorina, lakokò na nigbati gbogbo enia gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, ati oniruru orin gbogbo, gbogbo enia, orilẹ, ati ède wolẹ, nwọn si tẹriba fun ere wura na ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.

Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Àìgbọràn Kan Àwọn Ọ̀rẹ́ Daniẹli Mẹtẹẹta

8 Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn. 9 Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́. 10 Iwọ ọba ti paṣẹ pe, bi ẹnikẹni ba ti gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki o wolẹ ki o si tẹriba fun ere wura na. 11 Ẹnikẹni ti kò ba si wolẹ ki o tẹriba, ki a gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo. 12 Awọn ara Juda kan wà, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego ti iwọ fi ṣe olori ọ̀ran igberiko Babeli: Ọba, awọn ọkunrin wọnyi kò kà ọ si, nwọn kò sìn oriṣa rẹ, nwọn kò si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ. 13 Nigbana ni Nebukadnessari ọba paṣẹ ni ibinu ati irunu rẹ̀, pe, ki nwọn ki o mu Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego wá. Nigbana ni a si mu awọn ọkunrin wọnyi wá siwaju ọba. 14 Nebukadnessari dahùn, o si wi fun wọn pe, otitọ ha ni, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, pe, ẹnyin kò sìn oriṣa mi, ẹ kò si tẹriba fun ere wura na ti mo gbé kalẹ? 15 Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi. 16 Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego dahùn, nwọn si wi fun ọba pe, Nebukadnessari, kò tọ si wa lati fi èsi kan fun ọ nitori ọ̀ran yi. 17 Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba. 18 Ṣugbọn bi bẹ̃kọ, ki o ye ọ, ọba pe, awa kì yio sìn oriṣa rẹ, bẹ̃li awa kì yio si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.

Wọ́n Dá Ẹjọ́ Ikú fún Àwọn Ọ̀rẹ́ Daniẹli Mẹtẹẹta

19 Nigbana ni Nebukadnessari kún fun ibinu, àwọ oju rẹ̀ si yipada si Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego: o dahùn, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o da iná ileru na ki õru rẹ̀ gboná niwọn igba meje jù bi a ti imu u gboná ri lọ. 20 O si paṣẹ fun awọn ọkunrin ani awọn alagbara julọ ninu ogun rẹ̀ pe ki nwọn ki o di Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ki nwọn ki o si sọ wọn sinu iná ileru na ti njo. 21 Nigbana ni a dè awọn ọkunrin wọnyi ti awọn ti agbáda, ṣokoto, ati ibori wọn, ati ẹwu wọn miran, a si gbé wọn sọ si ãrin iná ileru ti njo. 22 Nitorina bi aṣẹ ọba ti le to, ati bi ileru na si ti gboná gidigidi to, ọwọ iná na si pa awọn ọkunrin ti o gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, lọ. 23 Ṣugbọn awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ṣubu lulẹ ni didè si ãrin iná ileru ti njo. 24 Nigbana ni Nebukadnessari ọba warìri o si dide duro lọgan, o dahùn, o si wi fun awọn ìgbimọ rẹ̀ pe, awọn ọkunrin mẹta kọ a gbé sọ si ãrin iná ni didè? Nwọn si dahùn wi fun ọba pe, Lõtọ ni ọba. 25 O si dahùn wipe, Wò o, mo ri ọkunrin mẹrin ni titu, nwọn sì nrin lãrin iná, nwọn kò si farapa, ìrisi ẹnikẹrin si dabi ti Ọmọ Ọlọrun.

A Dá Àwọn Ọkunrin Mẹtẹẹta sílẹ̀ a sì gbé wọn ga

26 Nigbana ni Nebukadnessari sunmọ ẹnu-ọ̀na ileru na o dahùn o si wipe, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun Ọga-ogo, ẹ jade ki ẹ si wá. Nigbana ni Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, jade lati ãrin iná na wá. 27 Nigbana ni awọn ọmọ-alade, bãlẹ, balogun, ati awọn ìgbimọ ọba ti o pejọ ri pe iná kò lagbara lara awọn ọkunrin wọnyi, bẹ̃ni irun ori wọn kan kò jona, bẹ̃li aṣọ wọn kò si pada, õrùn iná kò tilẹ kọja lara wọn. 28 Nigbana ni Nebukadnessari dahùn o si wipe, Olubukún li Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹniti o rán angeli rẹ̀ ti o si gbà awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹ le e, nwọn si pa ọ̀rọ ọba da, nwọn si fi ara wọn jìn, ki nwọn ki o má ṣe sìn, tabi ki nwọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikarawọn. 29 Nitorina, emi paṣẹ pe, olukulùku enia, orilẹ, ati ède, ti o ba sọ ọ̀rọ odi si Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, a o ke e wẹwẹ, a o si sọ ile rẹ̀ di àtan: nitori kò si Ọlọrun miran ti o le gbà ni là bi iru eyi. 30 Nigbana ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego leke ni igberiko Babeli.

Danieli 4

Àlá Keji tí Nebukadinesari Lá

1 NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin. 2 O tọ loju mi lati fi àmi ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun, Ọga-ogo, ti ṣe si mi hàn. 3 Ami rẹ̀ ti tobi to! agbara iṣẹ iyanu rẹ̀ ti pọ̀ to! ijọba ainipẹkun ni ijọba rẹ̀, ati agbara ijọba rẹ̀ ati irandiran ni. 4 Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi: 5 Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi. 6 Nitorina ni mo ṣe paṣẹ lati mu gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli wá niwaju mi, ki nwọn ki o le fi itumọ alá na hàn fun mi. 7 Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi. 8 Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe, 9 Belteṣassari, olori awọn amoye, nitoriti mo mọ̀ pe ẹmi Ọlọrun mimọ mbẹ ninu rẹ, kò si si aṣiri kan ti o ṣoro fun ọ, sọ iran alá ti mo lá fun mi, ati itumọ rẹ̀. 10 Bayi ni iran ori mi lori akete mi; mo ri, si kiyesi i, igi kan duro li arin aiye, giga rẹ̀ si pọ̀ gidigidi. 11 Igi na si dagba, o si lagbara, giga rẹ̀ si kan ọrun, a si ri i titi de gbogbo opin aiye. 12 Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara. 13 Mo ri ninu iran ori mi lori akete mi, si kiye si i, oluṣọ, ani ẹni mimọ́ kan sọkalẹ lati ọrun wá; 14 O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀: 15 Ṣugbọn, fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ ninu ilẹ, ani pẹlu ide ninu irin ati idẹ ninu koriko tutu igbẹ; si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki o si ni ipin rẹ̀ ninu koriko ilẹ aiye pẹlu awọn ẹranko: 16 Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀. 17 Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀. 18 Alá yi li emi Nebukadnessari lá, njẹ nisisiyi, iwọ Belteṣassari, sọ itumọ rẹ̀ fun mi, bi gbogbo awọn ọlọgbọ́n ijọba mi kò ti le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn iwọ le ṣe e; nitori ẹmi Ọlọrun mimọ́ mbẹ lara rẹ.

Daniẹli Túmọ̀ Àlá náà

19 Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ. 20 Igi ti iwọ ri ti o si dagba, ti o si lagbara, eyi ti giga rẹ̀ kan ọrun, ti a si ri i de gbogbo aiye; 21 Eyi ti ewe rẹ̀ lẹwà, ti eso rẹ̀ si pọ̀, ninu eyi ti onjẹ si wà fun gbogbo ẹda, labẹ eyi ti awọn ẹranko igbẹ ngbe, lori ẹka eyi ti awọn ẹiyẹ oju-ọrun ni ibugbe wọn. 22 Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye. 23 Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀, 24 Ọba, itumọ rẹ̀ li eyi, ati eyiyi li aṣẹ Ọga-ogo, ti o wá sori ọba, oluwa mi: 25 Nwọn o le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ nwọn o si mu ki iwọ ki o jẹ koriko bi malu, nwọn o si mu ki iri ọrun sẹ̀ si ọ lara, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe Ọga-ogo ni iṣe olori ni ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u. 26 Ati gẹgẹ bi nwọn si ti paṣẹ pe ki nwọn ki o fi kukute gbòngbo igi na silẹ, ijọba rẹ yio jẹ tirẹ, lẹhin igbati o ba ti mọ̀ pe, ọrun ni iṣe olori. 27 Nitorina ọba, jẹ ki ìmọran mi ki o jẹ itẹwọgba lọdọ rẹ, ki o si fi ododo ja ẹ̀ṣẹ rẹ kuro, ati aiṣedẽde rẹ nipa fifi ãnu hàn fun awọn talaka; bi yio le mu alafia rẹ pẹ. 28 Gbogbo eyi de ba Nebukadnessari, ọba. 29 Lẹhin oṣu mejila, o nrin kiri lori ãfin ijọba Babeli. 30 Ọba si dahùn, o wipe, Ko ṣepe eyi ni Babeli nla, ti emi ti fi lile agbara mi kọ́ ni ile ijọba, ati fun ogo ọlanla mi? 31 Bi ọ̀rọ na si ti wà lẹnu ọba, ohùn kan fọ̀ lati ọrun wá, pe, Nebukadnessari, ọba, iwọ li a sọ fun; pe, a gba ijọba kuro lọwọ rẹ. 32 A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u. 33 Ni wakati kanna ni nkan na si ṣẹ si Nebukadnessari, a si le e kuro larin enia, o si jẹ koriko bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, titi irun ori rẹ̀ fi kún gẹgẹ bi iyẹ idì, ẽkana rẹ̀ si dabi ti ẹiyẹ.

Nebukadinesari Yin Ọlọrun Lógo

34 Li opin igba na, Emi Nebukadnessari si gbé oju mi soke si ọrun, oye mi si pada tọ̀ mi wá, emi si fi ibukún fun Ọga-ogo, mo yìn, mo si fi ọla fun ẹniti o wà titi lailai, ẹniti agbara ijọba rẹ̀ jẹ ijọba ainipẹkun, agbara ati ijọba rẹ̀ lati irandiran. 35 Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì? 36 Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ. 37 Nisisiyi, emi Nebukadnessari yìn, mo si gbé Ọba ọrun ga, mo si fi ọlá fun u, ẹniti gbogbo iṣẹ rẹ̀ iṣe otitọ, ati gbogbo ọ̀na rẹ̀ iṣe idajọ: ati awọn ti nrìn ninu igberaga, on le rẹ̀ wọn silẹ.

Danieli 5

Àsè Belṣsasari

1 BELṢASSARI, ọba se àse nla fun ẹgbẹrun awọn ijoye rẹ̀, o si nmu ọti-waini niwaju awọn ẹgbẹrun na. 2 Bi Belṣassari ti tọ́ ọti-waini na wò, o paṣẹ pe ki nwọn ki o mu ohun-elo wura, ati ti fadaka wá, eyiti Nebukadnessari baba rẹ̀, kó jade lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu wá, ki ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, ki o le ma muti ninu wọn. 3 Nigbana ni nwọn mu ohun-elo wura ti a ti kó jade lati inu tempili ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu wá; ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, si nmuti ninu wọn. 4 Nwọn nmu ọti-waini, nwọn si nkọrin ìyin si awọn oriṣa wura, ati ti fadaka, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta. 5 Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ enia kan jade wá, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa-fitila li ãfin ọba: ọba si ri ọwọ ti o kọwe na. 6 Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn. 7 Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba. 8 Nigbana ni gbogbo awọn amoye ọba wọle; ṣugbọn nwọn kò le kà iwe na, nwọn kò si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba. 9 Nigbana ni ẹ̀ru nla ba Belṣassari ọba gidigidi, oju rẹ̀ si yipada lori rẹ̀, ẹ̀ru si ba awọn ijoye rẹ̀. 10 Nitorina ni ayaba ṣe wọ ile-àse wá, nitori ọ̀ran ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; ayaba dahùn o si wipe, Ki ọba ki o pẹ́: má ṣe jẹ ki ìro-inu rẹ ki o dãmu rẹ, má si jẹ ki oju rẹ ki o yipada. 11 Ọkunrin kan mbẹ ni ijọba rẹ, lara ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà; ati li ọjọ baba rẹ, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun lara rẹ̀: ẹniti Nebukadnessari ọba, baba rẹ, ani ọba, baba rẹ fi ṣe olori awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ti awọn alafọṣẹ: 12 Niwọnbi ẹmi titayọ ati ìmọ, ati oye itumọ alá, oye ati já alọ́, ati lati ma ṣe itumọ ọ̀rọ ti o diju, gbogbo wọnyi li a ri lara Danieli na, ẹniti ọba fi orukọ Belteṣassari fun, njẹ nisisiyi jẹ ki a pè Danieli wá, on o si fi itumọ rẹ̀ hàn.

Daniẹli Túmọ̀ Àkọsílẹ̀ Náà

13 Nigbana ni a mu Danieli wá siwaju ọba. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Iwọ ni Danieli nì, ti iṣe ti inu awọn ọmọ igbekun Juda! awọn ẹniti ọba, baba mi kó lati ilẹ Juda wá? 14 Emi ti gburo rẹ pe ẹmi Ọlọrun mbẹ lara rẹ, ati pe, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n titayọ lara rẹ, 15 Njẹ nisisiyi, a ti mu awọn amoye, ati awọn ọlọgbọ́n wá siwaju mi, ki nwọn ki o le ka iwe yi, ati lati fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn nwọn kò le fi itumọ ọ̀ran na hàn: 16 Emi si gburo rẹ pe, iwọ le ṣe itumọ, iwọ si le tu ọ̀rọ ti o diju: njẹ nisisiyi, bi iwọ ba le ka iwe na, ti iwọ ba si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, a o wọ̀ ọ li aṣọ ododó, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a o si fi ọ jẹ olori ẹkẹta ni ijọba. 17 Nigbana ni Danieli dahùn, o si wi niwaju ọba pe, Jẹ ki ẹ̀bun rẹ gbe ọwọ rẹ, ki o si fi ẹsan rẹ fun ẹlomiran; ṣugbọn emi o ka iwe na fun ọba, emi o si fi itumọ rẹ̀ hàn fun u. 18 Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ: 19 Ati nitori ọlanla ti o fi fun u, gbogbo enia, orilẹ, ati ède gbogbo nwariri, nwọn si mbẹ̀ru niwaju rẹ̀: ẹniti o wù u, a pa, ẹniti o si wù u, a da si lãye; ẹniti o wù u, a gbé ga; ẹniti o si wú u, a rẹ̀ silẹ. 20 Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀: 21 A si le e kuro lãrin awọn ọmọ enia; a si ṣe aiya rẹ̀ dabi ti ẹranko, ibugbe rẹ̀ si wà lọdọ awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ; nwọn si fi koriko bọ́ ọ gẹgẹ bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara; titi on fi mọ̀ pe Ọlọrun Ọga-ogo ni iṣe alakoso ninu ijọba enia, on a si yàn ẹnikẹni ti o wù u ṣe olori rẹ̀. 22 Ati iwọ Belṣassari, ọmọ rẹ̀, iwọ kò rẹ̀ ọkàn rẹ silẹ, bi iwọ si tilẹ ti mọ̀ gbogbo nkan wọnyi; 23 Ṣugbọn iwọ gbé ara rẹ ga si Oluwa ọrun, nwọn si ti mu ohun-elo ile rẹ̀ wá siwaju rẹ, iwọ ati awọn ijoye rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn àle rẹ si ti nmu ọti-waini ninu wọn; iwọ si ti nkọrin iyìn si oriṣa fadaka, ati ti wura, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta, awọn ti kò riran, ti kò gbọran, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀: ṣugbọn Ọlọrun na, lọwọ ẹniti ẹmi rẹ wà, ati ti ẹniti gbogbo ọ̀na rẹ iṣe on ni iwọ kò bu ọlá fun. 24 Nitorina ni a ṣe rán ọwọ na lati ọdọ rẹ̀ wá; ti a si fi kọ iwe yi. 25 Eyiyi si ni iwe na ti a kọ, MENE, MENE, TEKELI, PERESINI. 26 Eyi ni itumọ ohun na: MENE, Ọlọrun ti ṣirò ijọba rẹ, o si pari rẹ̀. 27 TEKELI; A ti wọ̀n ọ wò ninu ọ̀ṣuwọn, iwọ kò si to. 28 PERESINI; A pin ijọba rẹ, a si fi fun awọn ara Media, ati awọn ara Persia. 29 Nigbana ni Belṣassari paṣẹ, nwọn si wọ̀ Danieli li aṣọ ododó, a si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a si ṣe ikede niwaju rẹ̀ pe, ki a fi i ṣe olori ẹkẹta ni ijọba. 30 Loru ijọ kanna li a pa Belṣassari, ọba awọn ara Kaldea. 31 Dariusi, ara Media si gba ijọba na, o si jẹ bi ẹni iwọn ọdun mejilelọgọta.

Danieli 6

Daniẹli ninu Ihò Kinniun

1 O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba; 2 Ati lori awọn wọnyi ni alakoso mẹta: Danieli si jẹ ọkan ninu wọn: ki awọn arẹ bãlẹ ki o le ma jiyin fun wọn, ki ọba ki o má ṣe ni ipalara. 3 Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba. 4 Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. 5 Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀. 6 Nigbana ni awọn alakoso ati awọn arẹ bãlẹ wọnyi pejọ pọ̀ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi bayi pe ki Dariusi ọba, ki o pẹ́. 7 Gbogbo awọn olori alakoso ijọba, awọn bãlẹ ati awọn arẹ bãlẹ, awọn ìgbimọ, ati olori ogun jọ gbìmọ pọ̀ lati fi ofin ọba kan lelẹ, ati lati paṣẹ lile kan, pe ẹnikẹni ti o ba bère nkan lọwọ Ọlọrun tabi eniakenia niwọn ọgbọ̀n ọjọ bikoṣepe lọwọ rẹ, ọba, a o gbé e sọ sinu ihò kiniun. 8 Njẹ nisisiyi, ọba, fi aṣẹ na lelẹ, ki o si fi ọwọ rẹ sinu iwe ki o máṣe yipada, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, eyi ti a kò gbọdọ pada. 9 Nigbana ni Dariusi fi ọwọ sinu iwe ati aṣẹ na. 10 Nigbati Danieli si ti mọ̀ pe a kọ iwe na tan, o wọ ile rẹ̀ lọ; (a si ṣi oju ferese yara rẹ̀ silẹ siha Jerusalemu) o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ nigba mẹta lõjọ, o gbadura, o si dupẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi on ti iṣe nigba atijọ ri. 11 Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi rìn wọle, nwọn si ri Danieli ngbadura, o si mbẹbẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀. 12 Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada. 13 Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ. 14 Nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi o si fi ọkàn rẹ̀ si Danieli lati gbà a silẹ: o si ṣe lãlã ati gbà a silẹ titi fi di igbati õrun wọ̀. 15 Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi pejọ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi fun ọba pe, Iwọ mọ̀, ọba, pe ofin awọn ara Media ati Persia ni pe: kò si aṣẹ tabi ofin ti ọba fi lelẹ ti a gbọdọ yipada. 16 Nigbana ni ọba paṣẹ, nwọn si mu Danieli wá, nwọn si gbé e sọ sinu iho kiniun. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, on o gbà ọ la. 17 A si yi okuta kan wá, nwọn si gbé e ka oju iho na; ọba si fi oruka edidi rẹ̀ sami si i, ati oruka edidi awọn ijoye rẹ̀, ki ohunkohun máṣe yipada nitori Danieli. 18 Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀. 19 Nigbana ni Ọba dide li afẹmọjumọ, o si yara kánkan lọ si ibi iho kiniun na. 20 Nigbati o si sunmọ iho na o fi ohùnrére ẹkun kigbe si Danieli: ọba dahùn o si wi fun Danieli pe, Danieli! iranṣẹ Ọlọrun alãye! Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, ha le gbà ọ lọwọ awọn kiniun bi? 21 Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ. 22 Ọlọrun mi ti ran angeli rẹ̀, o si dì awọn kiniun na lẹnu, ti nwọn kò fi le pa mi lara: gẹgẹ bi a ti ri mi lailẹṣẹ niwaju rẹ̀; ati niwaju rẹ pẹlu, ọba, emi kò si ṣe ohun buburu kan. 23 Nigbana ni ọba yọ̀ gidigidi, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o fà Danieli jade kuro ninu iho. Bẹ̃li a si fa Danieli jade kuro ninu iho, a kò si ri ipalara lara rẹ̀, nitoriti o gbà Ọlọrun rẹ̀ gbọ́. 24 Ọba si paṣẹ, pe ki a mu awọn ọkunrin wọnni wá, ti o fi Danieli sùn, nwọn si gbé wọn sọ sinu iho kiniun, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn aya wọn. Ki nwọn ki o to de isalẹ iho, awọn kiniun bori wọn, nwọn si fọ egungun wọn tũtu. 25 Nigbana ni Dariusi, ọba kọwe si gbogbo enia, orilẹ, ati ède ti o wà ni gbogbo aiye pe, Ki alafia ki o ma bi si i fun nyin. 26 Mo paṣẹ pe, Ni gbogbo igberiko ijọba mi, ki awọn enia ki o ma warìri, ki nwọn si ma bẹ̀ru niwaju Ọlọrun Danieli, nitoripe on li Ọlọrun alãye, on si duro lailai, ati ijọba rẹ̀, eyi ti a kì yio le parun ni, ati agbara ijọba rẹ̀ yio si wà titi de opin. 27 O ngbà ni, o si nyọ ni, o si nṣe iṣẹ-ami ati iṣẹ-iyanu li ọrun ati li aiye, ẹniti o gbà Danieli là lọwọ awọn kiniun. 28 Bẹ̃ni Danieli yi si nṣe rere ni igba ijọba Dariusi, ati ni igba ijọba Kirusi, ara Persia.

Danieli 7

Àlá Daniẹli Nípa Àwọn Ẹranko Mẹrin

1 LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na. 2 Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla. 3 Ẹranko mẹrin nla si ti inu okun jade soke, nwọn si yatọ si ara wọn. 4 Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u. 5 Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ. 6 Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u. 7 Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa. 8 Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.

Ìran Nípa Ẹni Ayérayé tó Jókòó lórí Ìtẹ́

9 Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná. 10 Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ. 11 Nigbana ni mo wò nitori ohùn ọ̀rọ nla ti iwo na nsọ: mo si wò titi a fi pa ẹranko na, a si pa ara rẹ̀ run, a si sọ ọ sinu ọwọ iná ti njo. 12 Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó. 13 Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀. 14 A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.

A Túmọ̀ Ìran náà fún Daniẹli

15 Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu. 16 Mo sunmọ ọkan ninu awọn ti o duro lapakan, mo si bi i lere otitọ gbogbo nkan wọnyi. Bẹ̃li o sọ fun mi, o si fi itumọ nkan wọnyi hàn fun mi. 17 Awọn ẹranko nla wọnyi, ti o jẹ mẹrin, li awọn ọba mẹrin ti yio dide li aiye. 18 Ṣugbọn awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo julọ yio gbà ijọba, nwọn o si jogun ijọba na lai, ani titi lailai. 19 Nigbana ni mo si nfẹ imọ̀ otitọ ti ẹranko kẹrin, eyiti o yatọ si gbogbo awọn iyokù, ti o lẹrù gidigidi, eyi ti ehin rẹ̀ jẹ irin, ti ẽkanna rẹ̀ jẹ idẹ, ti njẹ, ti nfọ tũtu, ti o si nfi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ. 20 Ati niti iwo mẹwa ti o wà li ori rẹ̀, ati omiran na ti o yọ soke, niwaju eyiti mẹta si ṣubu; ani iwo na ti o ni oju, ati ẹnu ti nsọ̀rọ ohun nlanla, eyi ti oju rẹ̀ si koro jù ti awọn ẹgbẹ rẹ̀ lọ. 21 Mo ri iwo kanna si mba awọn enia-mimọ́ jagun, o si bori wọn. 22 Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na. 23 Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu. 24 Ati iwo mẹwa, lati inu ijọba na wá ni ọba mẹwa yio dide: omiran kan yio si dide lẹhin wọn, on o si yàtọ si gbogbo awọn ti iṣaju, on o si bori ọba mẹta. 25 On o si ma sọ̀rọ nla si Ọga-ogo, yio si da awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo lagara, yio si rò lati yi akokò ati ofin pada; a o si fi wọn le e lọwọ titi fi di igba akokò kan, ati awọn akokò, ati idaji akokò. 26 Ṣugbọn awọn onidajọ yio joko, nwọn o si gbà agbara ijọba rẹ̀ lọwọ rẹ̀ lati fi ṣòfo, ati lati pa a run de opin. 27 Ati ijọba, ati agbara ijọba ati ipa gbogbo ijọba ni gbogbo abẹ-ọrun, li a o si fi fun enia awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo, ijọba ẹniti iṣe ijọba ainipẹkun, ati gbogbo awọn alakoso ni yio ma sìn, ti nwọn o si ma tẹriba fun u. 28 Titi de ihinyi li opin ọ̀ran na. Bi o ṣe ti emi Danieli ni, igbero inu mi dãmu mi gidigidi, oju mi si yipada lori mi: ṣugbọn mo pa ọran na mọ́ li ọkàn mi.

Danieli 8

Ìran tí Daniẹli Rí Nípa Àgbò ati Ewúrẹ́

1 LI ọdun kẹta ijọba Belṣassari ọba, iran kan fi ara hàn fun mi, ani emi Danieli, lẹhin iran ti emi ri ni iṣaju. 2 Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai. 3 Mo si gbé oju mi soke, mo si ri, si kiye si i, àgbo kan ti o ni iwo meji duro lẹba odò na: iwo mejeji na si ga, ṣugbọn ekini ga jù ekeji lọ, eyiti o ga jù li o jade kẹhin. 4 Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla. 5 Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀. 6 O si tọ̀ àgbo ti o ni iwo meji na wá, eyi ti mo ti ri ti o duro lẹba odò na, o si fi irunu agbara sare si i. 7 Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀. 8 Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun. 9 Ati lati inu ọkan ninu wọn ni iwo kekere kan ti jade, ti o si di alagbara gidigidi, si iha gusu, ati si iha ila-õrùn, ati si iha ilẹ ogo. 10 O si di alagbara, titi de ogun ọrun, o si bì ṣubu ninu awọn ogun ọrun, ati ninu awọn irawọ si ilẹ, o si tẹ̀ wọn mọlẹ. 11 Ani o gbé ara rẹ̀ ga titi de ọdọ olori awọn ogun na pãpa, a si ti mu ẹbọ ojojumọ kuro lọdọ rẹ̀, a si wó ibujoko ìwa-mimọ́ rẹ̀ lulẹ. 12 A si fi ogun le e lọwọ pẹlu ẹbọ ojojumọ nitori irekọja, o si ja otitọ lulẹ, o si nṣe eyi, o si nri rere. 13 Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to? 14 O si wi fun mi pe, titi fi di ọgbọnkanla le ọgọrun ti alẹ ti owurọ: nigbana ni a o si yà ibi-mimọ́ si mimọ́.

Angẹli Gabrieli Túmọ̀ Ìran Náà

15 O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin. 16 Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na. 17 Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe. 18 Njẹ bi o ti mba mi sọ̀rọ, mo dãmu, mo si doju bolẹ: ṣugbọn o fi ọwọ kàn mi, o si gbé mi dide duro si ipò mi. 19 O si wipe, kiyesi i, emi o mu ọ mọ̀ ohun ti yio ṣe ni igba ikẹhin ibinu na: nitoripe, akokò igba ikẹhin ni eyi iṣe. 20 Agbò na ti iwọ ri ti o ni iwo meji nì, awọn ọba Media ati Persia ni nwọn. 21 Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini. 22 Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀. 23 Li akokò ikẹhin ijọba wọn, nigbati awọn oluṣe irekọja ba de ni kíkun, li ọba kan yio dide, ti oju rẹ̀ buru, ti o si moye ọ̀rọ arekereke. 24 Agbara rẹ̀ yio si le gidigidi, ṣugbọn kì iṣe agbara ti on tikararẹ̀: on o si ma ṣe iparun ti o yani lẹnu, yio si ma ri rere ninu iṣẹ, yio si pa awọn alagbara ati awọn enia ẹni-mimọ́ run. 25 Ati nipa arekereke rẹ̀ yio si mu ki iṣẹ ẹ̀tan ṣe dẽde lọwọ rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga li ọkàn rẹ̀, lojiji ni yio si pa ọ̀pọlọpọ run, yio dide si olori awọn ọmọ-alade nì; ṣugbọn on o ṣẹ́ laisi ọwọ. 26 Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni. 27 Arẹ̀ si mu emi Danieli, ara mi si ṣe alaida niwọn ọjọ melokan; lẹhin na, mo dide, mo si nṣe iṣẹ ọba; ẹ̀ru si bà mi, nitori iran na, ṣugbọn kò si ẹni ti o fi ye mi.

Danieli 9

Daniẹli Gbadura fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 LI ọdun kini Dariusi, ọmọ Ahasuerusi, lati iru-ọmọ awọn ara Media wá, ti a fi jọba lori ilẹ-ọba awọn ara Kaldea; 2 Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li emi Danieli fiyesi lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi ti ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah, woli wá, pe adọrin ọdun li on o mu pé lori idahoro Jerusalemu. 3 Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma ṣafẹri nipa adura ati ẹ̀bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ẽru. 4 Emi si gbadura si Oluwa Ọlọrun mi, mo si ṣe ijẹwọ mi, mo si wipe, Oluwa, iwọ Ọlọrun ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ́ fun awọn ti o fẹ ẹ, ati fun awọn ti o pa ofin rẹ̀ mọ́; 5 Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ: 6 Bẹ̃li awa kò si fi eti si awọn iranṣẹ rẹ, awọn woli, ti o sọ̀rọ li orukọ rẹ fun awọn ọba wa, awọn ọmọ-alade wa, ati awọn baba wa, ati fun gbogbo awọn enia ilẹ wa. 7 Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ. 8 Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ. 9 Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i; 10 Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá. 11 Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i. 12 On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu. 13 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ. 14 Nitorina li Oluwa ṣe fiyesi ibi na, ti o si mu u wá sori wa; nitoripe olododo li Oluwa Ọlọrun wa ni gbogbo iṣẹ rẹ̀ ti o nṣe: ṣugbọn awa kò gbà ohùn rẹ̀ gbọ́. 15 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, iwọ ti o ti fi ọwọ agbara mu awọn enia rẹ jade lati Egipti wá, ti iwọ si ti gba orukọ fun ara rẹ gẹgẹ bi o ti wà loni: awa ti ṣẹ̀, awa si ti ṣe buburu gidigidi. 16 Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka. 17 Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa. 18 Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla. 19 Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.

Gabraeli Túmọ̀ Àlá náà

20 Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi. 21 Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ. 22 O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ. 23 Ni ipilẹṣẹ ẹ̀bẹ rẹ li ọ̀rọ ti jade wá, emi si wá lati fi hàn fun ọ, nitoriti iwọ iṣe ayanfẹ gidigidi: nitorina, moye ọ̀ran na, ki o si kiyesi iran na. 24 Adọrin ọ̀sẹ li a pinnu sori awọn enia rẹ, ati sori ilu mimọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi di ẹ̀ṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedẽde ati lati mu ododo ainipẹkun wá ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yàn Ẹni-mimọ́ julọ nì. 25 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀, ki o si ye ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ na lati tun Jerusalemu ṣe, ati lati tun u kọ́, titi de igba ọmọ-alade Ẹni-ororo na, yio jẹ ọ̀sẹ meje, ati ọ̀sẹ mejilelọgọta: a o si tun igboro rẹ̀ ṣe, a o mọdi rẹ̀, ṣugbọn ni igba wahala. 26 Lẹhin ọ̀sẹ mejilelọgọta na li a o ke Ẹni-ororo na kuro, kì yio si si ẹnikan fun u, ati awọn enia ọmọ-alade kan ti yio wá ni yio pa ilu na ati ibi-mimọ́ run; opin ẹniti mbọ yio dabi ikún omi, ati ogun titi de opin, eyi ni ipari idahoro. 27 On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọlọpọ niwọn ọ̀sẹ kan: ati lãrin ọ̀sẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yio si duro lori ibi-mimọ́ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro.

Danieli 10

Ìran tí Daniẹli Rí ní Odò Hiddekeli

1 LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na. 2 Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako. 3 Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe. 4 Nigbati o di ọjọ kẹrinlelogun oṣu kini, bi mo ti wà li eti odò nla, ti ijẹ Hiddekeli; 5 Nigbana ni mo gbé oju mi soke, mo wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti o wọ̀ aṣọ àla, ẹ̀gbẹ ẹniti a fi wura Ufasi daradara dì li àmure: 6 Ara rẹ̀ pẹlu dabi okuta berili, oju rẹ̀ si dabi manamána, ẹyinju rẹ̀ dabi iná fitila, apa ati ẹsẹ rẹ̀ li awọ̀ ti o dabi idẹ ti a wẹ̀ dan, ohùn ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ si dabi ohùn ijọ enia pupọ. 7 Emi Danieli nikanṣoṣo li o si ri iran na, awọn ọkunrin ti o si wà pẹlu mi kò ri iran na; ṣugbọn ìwariri nlanla dà bò wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi sá lọ lati fi ara wọn pamọ́. 8 Nitorina emi nikan li o kù, ti mo si ri iran nla yi, kò si kù agbara ninu mi: ẹwà mi si yipada lara mi di ibajẹ, emi kò si lagbara mọ. 9 Sibẹ mo gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀: nigbati mo si gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀, nigbana ni mo dãmu, mo si wà ni idojubolẹ̀. 10 Sa si kiyesi i, ọwọ kan kàn mi, ti o gbé mi dide lori ẽkun mi, ati lori atẹlẹwọ mi. 11 O si wi fun mi pe, Danieli, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, ki oye ọ̀rọ ti mo nsọ fun ọ ki o ye ọ, ki o si duro ni ipò rẹ: nitoripe iwọ li a rán mi si nisisiyi. Nigbati on ti sọ̀rọ bayi fun mi, mo dide duro ni ìwariri. 12 Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ. 13 Ṣugbọn balogun ijọba Persia nì dè mi li ọ̀na li ọjọ mọkanlelogun: ṣugbọn, wò o, Mikaeli, ọkan ninu awọn olori balogun wá lati ràn mi lọwọ: emi si di ipò mi mu lọdọ awọn ọba Persia. 14 Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe. 15 Nigbati o si ti sọ iru ọ̀rọ bayi fun mi tan, mo dojukọ ilẹ mo si yadi. 16 Si wò o, ẹnikan ti jijọ rẹ̀ dabi ti awọn ọmọ enia fi ọwọ kan ète mi: nigbana ni mo ya ẹnu mi, mo si fọhùn, mo si wi fun ẹniti o duro tì mi pe, oluwa mi, niti iran na, irora mi pada sinu mi, emi kò si lagbara mọ. 17 Nitoripé bawo ni ọmọ-ọdọ oluwa mi yi yio ti ṣe le ba oluwa mi yi sọ̀rọ? ṣugbọn bi o ṣe temi ni, lojukanna, agbara kò kù ninu mi, bẹ̃ni kò si kù ẽmi ninu mi. 18 Nigbana ni ẹnikan ti o ni aworan enia wá o si tun fi ọwọ tọ́ mi, o si mu mi lara le, 19 O si wipe, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, má bẹ̀ru: alafia ni fun ọ, mu ara le. Ani mu ara le, Nigbati on ba mi sọ̀rọ, a si mu mi lara le, mo si wipe, Ki oluwa mi ki o ma sọ̀rọ, nitoriti iwọ ti mu mi lara le. 20 Nigbana ni o wipe, Iwọ, ha mọ̀ idi ohun ti mo tọ̀ ọ wá si? nisisiyi li emi o si yipada lọ iba balogun Persia jà: nigbati emi ba si jade lọ, kiyesi i, balogun Hellene yio wá. 21 Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.

Danieli 11

1 PẸLUPẸLU li ọdun kini Dariusi ara Media, emi pãpa duro lati mu u lọkàn le, ati lati fi idi rẹ̀ kalẹ. 2 Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.

Ìjọba Egypti ati ti Siria

3 Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀. 4 Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi. 5 Ọba iha gusu yio si lagbara; ṣugbọn ọkan ninu awọn balogun rẹ̀, on o si lagbara jù u lọ, yio si jọba, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba nla. 6 Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja. 7 Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori. 8 On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa. 9 On o si lọ si ijọba ọba gusu, ṣugbọn yio yipada si ilẹ ontikararẹ̀. 10 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀. 11 Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ. 12 Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi. 13 Nitoripe ọba ariwa yio si yipada, yio si kó ọ̀pọlọpọ enia jọ ti yio pọ̀ jù ti iṣaju lọ, yio si wá lẹhin ọdun melokan pẹlu ogun nla, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀. 14 Li akoko wọnni li ọ̀pọlọpọ yio si dide si ọba gusu; awọn ọlọ̀tẹ ninu awọn enia rẹ̀ yio si gbé ara wọn ga lati fi ẹsẹ iran na mulẹ pẹlu: ṣugbọn nwọn o ṣubu. 15 Bẹ̃li ọba ariwa yio si wá, yio si mọdi, yio si gbà ilu olodi; apá ogun ọba gusu kì yio le duro, ati awọn ayanfẹ enia rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si agbara lati da a duro. 16 Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun. 17 On o si gbé oju rẹ̀ soke lati wọ̀ ọ nipa agbara gbogbo ijọba rẹ̀, yio si ba a dá majẹmu, bẹ̃ni yio ṣe; on o si fi ọmọbinrin awọn obinrin fun u, lati bà a jẹ: ṣugbọn on kì yio duro, bẹ̃ni kì yio si ṣe tirẹ̀. 18 Lẹhin eyi, yio kọ oju rẹ̀ si erekuṣu wọnni, yio si gbà ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn balogun kan fun ara rẹ̀, yio fi opin si ẹ̀gan rẹ̀: ati nipò eyi, yio mu ẹ̀gan rẹ̀ pada wá sori ara rẹ̀. 19 Nigbana ni yio si yi oju rẹ̀ pada si ilu olodi ontikararẹ̀: ṣugbọn yio kọsẹ, yio si ṣubu, a kì yio si ri i mọ. 20 Nigbana ni ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀ ti yio mu agbowode kan rekọja ninu ogo ijọba (ilẹ Juda): ṣugbọn niwọn ijọ melokan li a o si pa a run, kì yio ṣe nipa ibinu tabi loju ogun.

Ọba Burúkú tí Ó Jẹ ní Siria

21 Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba. 22 Ogun ti mbò ni mọlẹ li a o fi bò wọn mọlẹ niwaju rẹ̀, a o si fọ ọ tũtu, ati pẹlu ọmọ-alade majẹmu kan. 23 Ati lẹhin igbati a ba ti ba a ṣe ipinnu tan, yio fi ẹ̀tan ṣiṣẹ: yio si gòke lọ, yio si fi enia diẹ bori. 24 Yio si wọ̀ gbogbo ibi igberiko ọlọra; yio si ṣe ohun ti awọn baba rẹ̀ kò ṣe ri, tabi awọn baba nla rẹ̀; yio si fọn ikogun, ìfa, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ ká si ãrin wọn: yio si gbèro tẹlẹ si ilu olodi, ani titi akokò kan. 25 Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i. 26 Awọn ẹniti o jẹ ninu adidùn rẹ̀ ni yio si pa a run, ogun rẹ̀ yio si tàn kalẹ; ọ̀pọlọpọ ni yio si ṣubu ni pipa. 27 Ọkàn awọn ọba mejeji wọnyi ni yio wà lati ṣe buburu, nwọn o si mã sọ̀rọ eké lori tabili kan, ṣugbọn kì yio jẹ rere; nitoripe opin yio wà li akokò ti a pinnu. 28 Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀. 29 Yio si pada wá li akokò ti a pinnu, yio si wá si iha gusu; ṣugbọn kì yio ri bi ti iṣaju, ni ikẹhin. 30 Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ. 31 Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ. 32 Ati iru awọn ti nṣe buburu si majẹmu nì ni yio fi ọ̀rọ ipọnni mu ṣọ̀tẹ: ṣugbọn awọn enia ti o mọ̀ Ọlọrun yio mu ọkàn le, nwọn o si ma ṣe iṣẹ agbara. 33 Awọn ti o moye ninu awọn enia yio ma kọ́ ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn nwọn o ma ti ipa oju idà ṣubu, ati nipa iná, ati nipa igbekun, ati nipa ikogun nijọmelo kan. 34 Njẹ nisisiyi, nigbati nwọn o ṣubu, a o fi iranlọwọ diẹ ràn wọn lọwọ: ṣugbọn ọ̀pọlọpọ ni yio fi ẹ̀tan fi ara mọ́ wọn. 35 Awọn ẹlomiran ninu awọn ti o moye yio si ṣubu, lati dan wọn wò, ati lati wẹ̀ wọn mọ́, ati lati sọ wọn di funfun, ani titi fi di akokò opin: nitoripe yio wà li akokò ti a pinnu. 36 Ọba na yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga, yio si gbéra rẹ̀ ga jù gbogbo ọlọrun lọ, yio si ma sọ̀rọ ohun iyanu si Ọlọrun awọn ọlọrun, yio si ma ṣe rere titi a o fi pari ibinu: nitori a o mu eyi ti a ti pinnu rẹ̀ ṣẹ. 37 Bẹ̃li on kì yio si kà Ọlọrun awọn baba rẹ̀ si, tabi ifẹ awọn obinrin, on kì yio si kà ọlọrun kan si: nitoriti yio gbé ara rẹ̀ ga jù ẹni gbogbo lọ. 38 Ṣugbọn ni ipò rẹ̀, yio ma bu ọlá fun ọlọrun awọn ilu olodi, ani ọlọrun kan ti awọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ri ni yio ma fi wura, ati fadaka, ati okuta iyebiye, ati ohun daradara bu ọlá fun. 39 Bẹ̃ gẹgẹ ni yio ṣe ninu ilu olodi wọnni ti o lagbara julọ nipa iranlọwọ ọlọrun ajeji, ẹniti o jẹ́wọ rẹ̀ ni yio fi ogo fun, ti yio si mu ṣe alakoso ọ̀pọlọpọ, yio si pín ilẹ fun li ère. 40 Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja. 41 Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni. 42 On o si nà ọwọ rẹ̀ jade si ilẹ wọnni pẹlu, ilẹ Egipti kì yio si là a. 43 Ṣugbọn on o lagbara lori iṣura wura, ati ti fadaka, ati lori gbogbo ohun daradara ni ilẹ Egipti: ati awọn ara Libia, awọn ara Etiopia yio si wà lẹhin rẹ̀. 44 Ṣugbọn ìhin lati ila-õrùn, ati lati iwọ-õrùn wá yio dãmu rẹ̀: nitorina ni yio ṣe fi ìbinu nla jade lọ lati ma parun, ati lati mu ọ̀pọlọpọ kuro patapata. 45 On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.

Danieli 12

Àkókò Ìkẹyìn

1 LI akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akokò wahala yio si wà, iru eyi ti kò ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe. 2 Ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn ti o sùn ninu erupẹ ilẹ ni yio ji, awọn miran si ìye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati ẹ̀gan ainipẹkun. 3 Awọn ọlọgbọ́n yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu: awọn ti o si nyi ọ̀pọlọpọ pada si ododo yio si ma tàn bi irawọ̀ lai ati lailai. 4 Ṣugbọn iwọ, Danieli sé ọ̀rọ na mọhun, ki o si fi edidi di iwe na, titi fi di igba ikẹhin: ọ̀pọlọpọ ni yio ma wadi rẹ̀, ìmọ yio si di pupọ. 5 Nigbana ni emi Danieli wò, si kiyesi i, awọn meji miran si duro: ọ̀kan lapa ihín eti odò, ati ekeji lapa ọhún eti odò. 6 Ẹnikan si wi fun ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla ti o duro lori omi odò pe, opin ohun iyanu wọnyi yio ti pẹ to? 7 Emi si gbọ́, ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla, ti o duro loju omi odò na, o gbé ọwọ ọtún ati ọwọ òsi rẹ̀ si ọrun, o si fi Ẹniti o wà titi lai nì bura pe, yio jẹ akokò kan, awọn akokò, ati ãbọ akokò; nigbati yio si ti ṣe aṣepe ifunka awọn enia mimọ́, gbogbo nkan wọnyi li a o si pari. 8 Emi si gbọ́, ṣugbọn kò ye mi: nigbana ni mo wipe, Oluwa mi, kini yio ṣe ikẹhin wọnyi? 9 O si wipe, Ma ba ọ̀na rẹ lọ, Danieli, nitoriti a ti se ọ̀rọ na mọ sọhún, a si fi edidi di i titi fi di igba ikẹhin. 10 Ọ̀pọlọpọ li a o wẹ̀ mọ́, nwọn o si di funfun, a o si dan wọn wò: ṣugbọn awọn ẹni-buburu yio ma ṣe buburu: gbogbo awọn enia buburu kì yio kiyesi i; ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n ni yio kiyesi i. 11 Ati lati igba akokò ti a o mu ẹbọ ojojumọ kuro, ati lati gbé irira isọdahoro kalẹ, yio jẹ ẹgbẹrun ati igba le ãdọrun ọjọ. 12 Ibukún ni fun ẹniti o duro dè, ti o si de ẹgbẹrun, ati ọdurun le marundilogoji ọjọ nì. 13 Ṣugbọn iwọ ma ba ọ̀na rẹ lọ, titi opin yio fi de, iwọ o si simi, iwọ o si dide duro ni ipo rẹ ni ikẹhin ọjọ.

Hosea 1

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Hosea, ọmọ Beeri wá, li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi, ọba Israeli.

Iyawo Hosea ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

2 Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa. 3 O si lọ o si fẹ́ Gomeri ọmọbinrin Diblaimu; ẹniti o loyún, ti o si bi ọmọkunrin kan fun u. 4 Oluwa si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Jesreeli; nitori niwọ̀n igbà diẹ, emi o bẹ̀ ẹ̀jẹ Jesreeli wò li ara ile Jehu, emi o si mu ki ijọba ile Israeli kasẹ̀. 5 Yio si ṣe li ọjọ na, li emi o ṣẹ́ ọrun Israeli ni afonifojì Jesreeli. 6 O si tún loyún, o si bi ọmọbinrin kan. Ọlọrun si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ li Loruhama: nitori emi kì yio tún ma ṣãnu fun ile Israeli mọ, nitoriti emi o mu wọn kuro. 7 Ṣugbọn emi o ṣãnu fun ile Juda, emi o si fi Oluwa Ọlọrun wọn gbà wọn là, emi kì yio si fi ọrun, tabi idà, tabi ogun, ẹṣin, tabi ẹlẹṣin gbà wọn là. 8 Nigbati o gbà ọmu li ẹnu Loruhama, o si loyún o si bi ọmọkunrin kan. 9 Nigbana ni Ọlọrun wipe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loammi; nitori ẹnyin kì iṣe enia mi, emi kì yio si ṣe Ọlọrun nyin.

A óo Ra Israẹli Pada

10 Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio ri bi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n ti a kò si lè ikà; yio si ṣe, ni ibi ti a gbe ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, ibẹ̀ li a o gbe wi fun wọn pe, Ẹnyin li ọmọ Ọlọrun alãyè. 11 Nigbana ni a o kó awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Israeli jọ̀ pọ̀, nwọn o si yàn olori kan fun ara wọn, nwọn o si jade kuro ni ilẹ na: nitori nla ni ọjọ Jesreeli yio jẹ.

Hosea 2

1 Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama.

Gomeri Alaiṣootọ–Israẹli Alaiṣootọ

2 Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀. 3 Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú. 4 Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère. 5 Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi. 6 Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ. 7 On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ. 8 Nitori on kò ti mọ̀ pe emi li ẹniti o fun u li ọkà, ati ọti-waini titun, ati ororo; ti mo si mu fàdakà ati wurà rẹ̀ pọ̀ si i, ti nwọn fi ṣe Baali. 9 Nitorina li emi o ṣe padà, emi o si mu ọkà mi kuro li akokò rẹ̀, ati ọti-waini mi ni igbà rẹ̀, emi o si gbà irun agùtan ati ọgbọ̀ mi padà, ti mo ti fi fun u lati bò ihòho rẹ̀. 10 Nisisiyi li emi o ṣi itiju rẹ̀ silẹ li oju awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ẹnikẹni kì yio si gbà a lọwọ mi. 11 Emi o si mu ki gbogbo ayọ̀ rẹ̀ de opin, ọjọ asè rẹ̀, oṣù titun rẹ̀, ati ọjọ isimi rẹ̀, gbogbo ọjọ ọ̀wọ rẹ̀. 12 Emi o si pa ajàra rẹ̀ ati igi ọpọ̀tọ rẹ̀ run, niti awọn ti o ti wipe, Awọn wọnyi li èrè mi ti awọn ayànfẹ́ mi ti fi fun mi; emi o si sọ wọn di igbo, awọn ẹranko igbẹ yio si jẹ wọn. 13 Emi o si bẹ̀ ọjọ Baalimu wò li ara rẹ̀, ninu eyiti on fi turari joná fun wọn, ti on si fi oruka eti, ati ohun ọ̀ṣọ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọṣọ, ti on si tọ̀ awọn ayànfẹ́ lẹhìn lọ, ti on si gbagbe mi, ni Oluwa wi.

Ìfẹ́ OLUWA sí Àwọn Eniyan Rẹ̀

14 Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mu u wá si aginjù, emi o si sọ̀rọ itùnu fun u. 15 Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá. 16 Yio si ṣe li ọjọ na, iwọ o pè mi ni Iṣi; iwọ kì yio si pè mi ni Baali mọ, ni Oluwa wi, 17 Nitori emi o mu orukọ awọn Baali kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si fi orukọ wọn ranti wọn mọ́. 18 Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu. 19 Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu. 20 Emi o tilẹ fẹ́ ọ fun ara mi ni otitọ, iwọ o si mọ̀ Oluwa. 21 Yio si ṣe li ọjọ na, emi o dahùn, emi o dá awọn ọrun li ohùn, nwọn o si da aiye lohùn; li Oluwa wi. 22 Ilẹ yio si dá ọkà, ati ọti-waini, ati ororo, li ohùn; nwọn o si dá Jesreeli li ohùn. 23 Emi o si gbìn i fun ara mi lori ilẹ, emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ti ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Iwọ li enia mi; on o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi.

Hosea 3

Hosea ati Obinrin Alaiṣootọ

1 OLUWA sí wi fun mi pe, Tun lọ, fẹ́ obinrin kan ti iṣe olùfẹ́ ọrẹ rẹ̀, ati panṣagà, gẹgẹ bi ifẹ Oluwa si awọn ọmọ Israeli, ti nwò awọn ọlọrun miràn, ti nwọn si nfẹ́ akàra eso àjara. 2 Bẹ̃ni mo rà a fun ara mi ni fadakà mẹ̃dogun, ati homeri barli kan pẹlu ãbọ̀: 3 Mo si wi fun u pe, Iwọ o ba mi gbe li ọjọ pupọ̀; iwọ kì yio si hùwa agbère, iwọ kì yio si jẹ ti ọkunrin miràn: bẹ̃li emi o jẹ tirẹ pẹlu. 4 Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu. 5 Lẹhìn na awọn ọmọ Israeli yio padà, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa, ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhìn.

Hosea 4

OLUWA Fi Ẹ̀sùn Kan Israẹli

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na. 2 Nipa ibura, ati eke, ati ipani, ati olè, ati iṣe panṣaga, nwọn gbìjà, ẹ̀jẹ si nkàn ẹ̀jẹ. 3 Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu.

Ọlọrun Fi Ẹ̀sùn Kan Àwọn Àlùfáà

4 Ṣugbọn má jẹ ki ẹnikẹni ki o jà, tabi ki o ba ẹnikeji rẹ̀ wi: nitori awọn enia rẹ dabi awọn ti mba alufa jà. 5 Iwọ o si ṣubu li ọ̀san, woli yio si ṣubu pẹlu rẹ li alẹ, emi o si ké iya rẹ kuro. 6 A ké awọn enia mi kuro nitori aini ìmọ: nitori iwọ ti kọ̀ ìmọ silẹ, emi o si kọ̀ ọ, ti iwọ kì yio ṣe alufa mi mọ: niwọ̀n bi iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu o gbagbe awọn ọmọ rẹ. 7 Bi a ti mu wọn pọ̀ si i to, bẹ̃ na ni nwọn si dẹ̀ṣẹ si mi to: nitorina emi o yi ogo wọn padà si itìju. 8 Nwọn jẹ ẹ̀ṣẹ awọn enia mi, nwọn si gbe ọkàn wọn si aiṣedẽde wọn. 9 Yio si ṣe, gẹgẹ bi enia, bẹ̃li alufa: emi o si bẹ̀ wọn wò nitori ọ̀na wọn, emi o si san èrè iṣẹ wọn padà fun wọn. 10 Nwọn o si jẹ, nwọn kì o si yó: nwọn o ṣe agbère, nwọn kì o si rẹ̀: nitori nwọn ti fi ati-kiyesi Oluwa silẹ.

OLUWA Kọ Ìbọ̀rìṣà

11 Agbère ati ọti-waini, ati ọti-waini titun a ma gbà enia li ọkàn. 12 Awọn enia mi mbère ìmọ lọwọ igi wọn, ọpá wọn si nfi hàn fun wọn: nitori ẹmi agbère ti mu wọn ṣìna, nwọn si ti ṣe agbère lọ kuro labẹ Ọlọrun wọn. 13 Nwọn rubọ lori awọn oke-nla, nwọn si sun turari lori awọn oke kékèké, labẹ igi oaku ati igi poplari ati igi ẹlmu, nitoriti ojìji wọn dara: nitorina awọn ọmọbinrin nyin yio ṣe agbère, ati awọn afẹ́sọnà nyin yio ṣe panṣagà. 14 Emi kì yio ba awọn ọmọbinrin nyin wi nigbati nwọn ba ṣe agbère, tabi awọn afẹ́sọnà nyin nigbati nwọn ba ṣe panṣagà: nitori nwọn yà si apakan pẹlu awọn agbère, nwọn si mba awọn panṣagà rubọ̀: nitorina awọn enia ti kò ba moye yio ṣubu. 15 Bi iwọ, Israeli, ba ṣe agbère, máṣe jẹ ki Juda ṣẹ̀; ẹ má si wá si Gilgali, bẹ̃ni ki ẹ má si goke lọ si Bet-afeni, bẹ̃ni ki ẹ má si bura pe, Oluwa mbẹ. 16 Nitori Israeli ṣe agidi bi ọmọ malu alagidi; nisisiyi Oluwa yio bọ́ wọn bi ọdọ-agùtan ni ibi ayè nla. 17 Efraimu dapọ̀ mọ òriṣa: jọwọ rẹ̀ si. 18 Ohun mimu wọn di kikan: nwọn ṣe agbère gidigidi; awọn olori rẹ̀ fẹ itìju, ẹ bun u li ayè. 19 Afẹfẹ ti dè e pẹlu mọ iyẹ́ apa rẹ̀, nwọn o si tíju nitori ẹbọ wọn.

Hosea 5

1 Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin alufa: si tẹtilelẹ ẹnyin ile Israeli; ki ẹ si gbọ́, ile ọba na; nitori idajọ kàn nyin, nitoriti ẹnyin ti jẹ ẹgẹ́ si Mispa, àwọn ti a nà silẹ lori Tabori. 2 Awọn ọlọ̀tẹ si jinlẹ ni pipanirun, emi o jẹ olùbawi gbogbo wọn. 3 Emi mọ̀ Efraimu, Israeli kò si pamọ́ fun mi: nitori nisisiyi, Efraimu, iwọ ṣe agbère, Israeli si dibajẹ.

Ìkìlọ̀ Hosea nípa Ìwà Ìbọ̀rìṣà

4 Iṣe wọn kì o jọ̀wọ wọn lati yipadà si Ọlọrun wọn: nitori ẹmi agbère wà lãrin wọn, nwọn kò si mọ̀ Oluwa. 5 A si rẹ̀ ogo Israeli silẹ loju ara rẹ̀; nitorina ni Israeli ati Efraimu yio ṣubu ninu aiṣedẽde wọn, Juda yio si ṣubu pẹlu wọn. 6 Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn. 7 Nwọn ti hùwa arekerekè si Oluwa: nitori nwọn ti bi ajèji ọmọ: nisisiyi li oṣù titun yio jẹ wọn run, pẹlu ipin wọn.

Ogun láàrin Juda ati Israẹli

8 Ẹ fun korneti ni Gibea, ati ipè ni Rama; kigbe kikan ni Bet-afeni, lẹhìn rẹ, iwọ Benjamini. 9 Efraimu yio di ahoro li ọjọ ibawi: ninu awọn ẹyà Israeli li emi ti fi ohun ti o wà nitõtọ hàn. 10 Awọn olori Juda dàbi awọn ti o yẹ̀ oju àla: lara wọn li emi o tú ibinu mi si bi omi. 11 A tẹ̀ ori Efraimu ba, a si ṣẹgun rẹ̀ ninu idajọ, nitoriti on mọ̃mọ̀ tẹ̀le ofin na. 12 Nitorina ni emi o ṣe dabi kòkoro aṣọ si Efraimu, ati si ile Juda bi idin. 13 Nigbati Efraimu ri arùn rẹ̀, ti Juda si ri ọgbẹ́ rẹ̀, nigbana ni Efraimu tọ̀ ara Assiria lọ, o si ranṣẹ si ọba Jarebu; ṣugbọn on kò le mu ọ lara da, bẹ̃ni kò le wò ọgbẹ́ rẹ jiná. 14 Nitori emi o dàbi kiniun si Efraimu, ati bi ọmọ kiniun si ile Juda, emi, ani emi o fàya, emi o si lọ, emi o mu lọ, ẹnikẹni kì yio si gbà a silẹ. 15 Emi o padà lọ si ipò mi, titi nwọn o fi jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ti nwọn o si wá oju mi: ninu ipọnju wọn, nwọn o wá mi ni kùtukùtu.

Hosea 6

Àwọn Eniyan náà Ṣe Ìrònúpìwàdà Èké

1 Ẹ wá, ẹ jẹ ki a yipadà si Oluwa: nitori o ti fà wa ya, on o si mu wa lara da; o ti lù wa, yio si tun wa dì. 2 Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀. 3 Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ. 4 Efraimu, kili emi o ṣe si ọ? Juda, kili emi o ṣe si ọ? nitori ore nyin dàbi ikuku owurọ̀, ati bi ìri kùtukùtu ti o kọja lọ. 5 Nitorina ni mo ṣe fi ãké ké wọn lati ọwọ awọn woli; mo ti fi ọ̀rọ ẹnu mi pa wọn: ki idajọ rẹ le ri bi imọlẹ ti o jade lọ. 6 Nitori ãnu ni mo fẹ́, ki iṣe ẹbọ; ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ. 7 Ṣugbọn bi Adamu nwọn ti dá majẹmu kọja: nibẹ̀ ni nwọn ti ṣẹ̀tan si mi. 8 Gileadi ni ilu awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ, a si ti fi ẹ̀jẹ bà a jẹ. 9 Ati gẹgẹ bi ọwọ́ olè iti lùmọ dè enia, bẹ̃ni ẹgbẹ́ awọn alufa fohùnṣọ̀kan lati pania li ọ̀na: nitori nwọn dá ẹ̀ṣẹ nla. 10 Mo ti ri ohun buburu kan ni ile Israeli: agbère Efraimu wà nibẹ̀, Israeli ti bajẹ. 11 Iwọ Juda pẹlu, on ti gbe ikorè kalẹ fun ọ, nigbati mo ba yi igbekun awọn enia mi padà.

Hosea 7

1 NIGBATI emi iba mu Israeli li ara dá, nigbana ni ẹ̀ṣẹ Efraimu fi ara hàn, ati ìwa-buburu Samaria; nitori nwọn ṣeké; olè si wọle, ọwọ́ olè si nkoni lode. 2 Nwọn kò si rò li ọkàn wọn pe, emi ranti gbogbo ìwa-buburu wọn: nisisiyi iṣẹ ara wọn duro yi wọn ka; nwọn wà niwaju mi.

Ọ̀tẹ̀ ní Ààfin

3 Nwọn fi ìwa-buburu wọn mu ki ọba yọ̀; nwọn si fi eké wọn mu awọn ọmọ-alade yọ̀. 4 Gbogbo nwọn ni panṣagà, bi ãrò ti alakàra mu gboná, ti o dawọ́ kikoná duro, lẹhìn igbati o ti pò iyẹ̀fun tan, titi yio fi wú. 5 Li ọjọ ọba wa, awọn ọmọ-alade ti fi oru ọti-waini mu u ṣaisàn; o nà ọwọ́ rẹ̀ jade pẹlu awọn ẹlẹgàn. 6 Nitori nwọn ti mura ọkàn wọn silẹ bi ãrò, nigbati nwọn ba ni buba: alakàra wọn sùn ni gbogbo oru; li owurọ̀ o jo bi ọwọ́-iná. 7 Gbogbo wọn gboná bi ãrò, nwọn ti jẹ awọn onidajọ wọn run; gbogbo ọba wọn ṣubu: kò si ẹnikan ninu wọn ti o ke pè mi.

Israẹli ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè

8 Efraimu, on ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn enia na; Efraimu ni akàra ti a kò yipadà. 9 Awọn alejò ti jẹ agbara rẹ̀ run, on kò si mọ̀: nitõtọ, ewú wà kakiri li ara rẹ̀, sibẹ̀ on kò mọ̀. 10 Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a. 11 Efraimu pẹlu dabi òpe adàba ti kò li ọkàn; nwọn kọ si Egipti, nwọn lọ si Assiria. 12 Nigbati nwọn o lọ, emi o nà àwọn mi le wọn; emi o mu wọn wá ilẹ bi ẹiyẹ oju-ọrun; emi o nà wọn, bi ijọ-enia wọn ti gbọ́. 13 Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi. 14 Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi. 15 Bi mo ti dì, ti mo si fun apa wọn li okun, sibẹ̀ nwọn nrò ibi si mi. 16 Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.

Hosea 8

OLUWA Bá Israẹli Wí nítorí Ìwà Ìbọ̀rìṣà

1 FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi. 2 Nwọn o kigbe si mi pe, Ọlọrun mi, awa Israeli mọ̀ ọ. 3 Israeli ti gbe ohunrere sọnù; ọta yio lepa rẹ̀. 4 Nwọn ti fi ọba jẹ, ṣugbọn kì iṣe nipasẹ̀ mi: nwọn ti jẹ olori, ṣugbọn emi kò si mọ̀: fàdakà wọn ati wurà wọn ni nwọn fi ṣe òriṣa fun ara wọn, ki a ba le ké wọn kuro. 5 Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ? 6 Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ. 7 Nitori nwọn ti gbìn ẹfũfũ, nwọn o si ka ãjà: kò ni igi ọka: irúdi kì yio si mu onjẹ wá: bi o ba ṣepe o mu wá, alejò yio gbe e mì. 8 A gbe Israeli mì: nisisiyi ni nwọn o wà lãrin awọn Keferi bi ohun-elò ninu eyiti inu-didùn kò si. 9 Nitori nwọn goke lọ si Assiria, kẹtẹ́kẹtẹ́ igbẹ́ nikan fun ara rẹ̀: Efraimu ti bẹ̀ awọn ọrẹ li ọ̀wẹ. 10 Nitõtọ, bi nwọn tilẹ ti bẹ̀ ọ̀wẹ lãrin awọn orilẹ-ède, nisisiyi li emi o ko wọn jọ, nwọn o si kãnu diẹ fun ẹrù ọba awọn ọmọ-alade. 11 Nitori Efraimu ti tẹ́ pẹpẹ pupọ̀ lati dẹ̀ṣẹ, pẹpẹ yio jẹ ohun atidẹ̀ṣẹ fun u. 12 Mo ti kọwe ohun pupọ̀ ti ofin mi si i, ṣugbọn a kà wọn si bi ohun ajèji. 13 Nwọn rubọ ẹran ninu ẹbọ ẹran mi, nwọn si jẹ ẹ; Oluwa kò tẹwọgbà wọn; nisisiyi ni yio ránti ìwa-buburu wọn, yio si bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò: nwọn o padà lọ si Egipti. 14 Nitori Israeli ti gbagbe Ẹlẹda rẹ̀, o si kọ́ tempili pupọ; Juda si ti sọ ilu olodi di pupọ̀: ṣugbọn emi o rán iná kan si ori awọn ilu rẹ̀, yio si jẹ awọn ãfin rẹ̀ wọnni run.

Hosea 9

Hosea Kéde Ìjìyà fún Israẹli

1 MÁṢE yọ̀, Israeli, fun ayọ̀, bi awọn enia miràn: nitori iwọ ti ṣe agbère lọ kuro lọdọ Ọlọrun rẹ, iwọ ti fẹ́ èrè lori ilẹ ipakà gbogbo. 2 Ilẹ ipakà ati ohun ifunti kì yio bọ́ wọn, ọti-waini titun yio si tan ninu rẹ̀. 3 Nwọn kì yio gbe inu ilẹ Oluwa; ṣugbọn Efraimu yio padà si Egipti, nwọn o si jẹ ohun aimọ́ ni Assiria. 4 Nwọn kì yio ta Oluwa li ọrẹ ọti-waini, bẹ̃ni nwọn kì yio mu u ni inu dùn: ẹbọ wọn yio ri fun wọn bi onjẹ awọn ti nṣọ̀fọ; gbogbo awọn ti o jẹ ninu rẹ̀ ni yio di alaimọ́: nitori onjẹ wọn kì yio wá si ile Oluwa fun ọkàn wọn. 5 Kili ẹnyin o ṣe li ọjọ ti o ni irònu, ati li ọjọ àse Oluwa? 6 Nitori, sa wò o, nwọn ti lọ nitori ikogun: Egipti yio kó wọn jọ, Memfisi yio sin wọn: ibi didara fun fadakà wọn li ẹgún-ọ̀gan yio jogun wọn: ẹgún yio wà ninu agọ wọn. 7 Ọjọ ibẹ̀wo de, ọjọ ẹsan de; Israeli yio mọ̀: aṣiwère ni woli na, ẹni ẹmi na nsinwin; nitori ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati irira nla na. 8 Olùṣọ Efraimu wà pẹlu Ọlọrun mi: ṣugbọn okùn pẹyẹpẹyẹ ni woli na li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati irira si ile Ọlọrun rẹ̀. 9 Nwọn ti ba ara wọn jẹ pupọ̀pupọ̀, bi li ọjọ Gibea: nitorina, on o ranti aiṣedẽde wọn, yio bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò.

Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Israẹli

10 Mo ri Israeli bi eso ajara li aginjù; mo ri awọn baba nyin bi akọpọ́n ninu igi ọpọ̀tọ li akọso rẹ̀: ṣugbọn nwọn tọ̀ Baal-peori lọ, nwọn si yà ara wọn si itiju nì; ohun irira wọn si ri gẹgẹ bi nwọn ti fẹ. 11 Bi o ṣe ti Efraimu, ogo wọn yio fò lọ bi ẹiyẹ, lati ibí, ati lati inu, ati lati iloyun. 12 Bi nwọn tilẹ tọ́ ọmọ wọn dàgba, ṣugbọn emi o gbà wọn li ọwọ wọn, ti kì yio fi kù enia kan; lõtọ, egbe ni fun wọn pẹlu nigbati mo ba kuro lọdọ wọn! 13 Efraimu, bi mo ti ri Tirusi, li a gbìn si ibi daradara: ṣugbọn Efraimu yio bi ọmọ rẹ̀ fun apania. 14 Fun wọn, Oluwa, li ohun ti iwọ o fun wọn. Fun wọn ni iṣẹnu ati ọmú gbigbẹ́.

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Israẹli

15 Gbogbo ìwa-buburu wọn mbẹ ni Gilgali; nitori nibẹ̀ ni mo korira wọn; nitori ìwa-buburu iṣe wọn, emi o le wọn kuro ni ile mi, emi kì yio fẹràn wọn mọ́; gbogbo ọmọ-alade wọn ni ọlọ̀tẹ. 16 A lù Efraimu, gbòngbo wọn gbẹ, nwọn kì yio so eso, bi nwọn tilẹ bi ọmọ, ṣugbọn emi o pa ãyò eso inu wọn.

Wolii Sọ̀rọ̀ Nípa Israẹli

17 Ọlọrun mi yio sọ wọn nù, nitoriti nwọn kò fetisi tirẹ̀; nwọn o si di alarinkiri lãrin awọn keferi.

Hosea 10

1 ÁJARA ofo ni Israeli, o nso eso fun ara rẹ̀; gẹgẹ bi ọ̀pọ eso rẹ̀ li o mu pẹpẹ pọ̀ si i; gẹgẹ bi didara ilẹ rẹ̀ ni nwọn yá ere daradara. 2 Ọkàn wọn dá meji; nisisiyi ni nwọn o jẹbi; on o wó pẹpẹ wọn lulẹ, on o si ba ere wọn jẹ. 3 Nitori nisisiyi ni nwọn o wipe, Awa kò li ọba, nitoriti awa kò bẹ̀ru Oluwa; njẹ kili ọba o ṣe fun wa? 4 Nwọn ti sọ ọ̀rọ, nwọn mbura eke ni didà majẹmu: bayi ni idajọ hù soke bi igi iwọ, ni aporo oko. 5 Nitori awọn ọmọ-malu Bet-afeni, awọn ti ngbe Samaria yio bẹ̀ru: nitori awọn enia ibẹ̀ yio ṣọ̀fọ lori rẹ̀, ati awọn baba-oloriṣà ibẹ̀ ti o yọ̀ lori rẹ̀, nitori ogo rẹ̀, nitori o ti lọ kuro lọdọ rẹ̀. 6 A o si mu u lọ si Assiria pẹlu ẹbùn fun Jarebu ọba: Efraimu yio gbà itiju, oju yio si tì Israeli nitori igbìmọ rẹ̀. 7 Bi o ṣe ti Samaria, a ké ọba rẹ̀ kuro bi ifõfõ loju omi. 8 Ibi giga Afeni pẹlu, ẹ̀ṣẹ Israeli, li a o parun; ẹgún ọ̀gan on oṣuṣu yio hù jade lori pẹpẹ wọn; nwọn o si wi fun awọn oke-nla pe, Bò wa mọlẹ; ati fun awọn oke kékèké pe, Wó lù wa.

OLUWA Kéde Ìdájọ́ lórí Israẹli

9 Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba? 10 Ifẹ inu mi ni ki nle nà wọn; a o si gbá awọn enia jọ si wọn, lati di ara wọn si ẹ̀ṣẹ wọn mejeji. 11 Efraimu si dabi ọmọ-malu ti a kọ́, ti o si fẹ́ lati ma tẹ ọkà; ṣugbọn emi rekọja li ori ọrùn rẹ̀ ti o ni ẹwà: emi o mu ki Efraimu gùn ẹṣin; Juda yio tú ilẹ, Jakobu yio si fọ́ ogulùtu rẹ̀. 12 Ẹ furùngbin fun ara nyin li ododo, ẹ ká li ãnu: ẹ tú ilẹ nyin ti a kò ro: nitori o to akokò lati wá Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rọ̀jo ododo si nyin. 13 Ẹnyin ti tulẹ ìwa-buburu, ẹnyin ti ká aiṣedẽde; ẹnyin ti jẹ eso eke: nitori iwọ gbẹkẹ̀le ọ̀na rẹ, ninu ọ̀pọlọpọ awọn alagbara rẹ. 14 Nitorina li ariwo yio dide ninu awọn enia rẹ, gbogbo awọn odi agbara rẹ li a o si bajẹ, bi Ṣalmani ti ba Bet-abeli jẹ li ọjọ ogun: a fọ́ iya tũtũ lori awọn ọmọ rẹ̀. 15 Bẹ̃ni Beteli yio ṣe si nyin, nitori ìwa-buburu nla nyin; ni kùtukùtu li a o ke ọba Israeli kuro patapata.

Hosea 11

Ìfẹ́ Ọlọrun sí Àwọn Eniyan Rẹ̀, Ọlọ̀tẹ̀

1 NIGBATI Israeli wà li ọmọde, nigbana ni mo fẹ́ ẹ, mo si pè ọmọ mi lati Egipti jade wá. 2 Bi nwọn ti pè wọn, bẹ̃ni nwọn lọ kuro lọdọ wọn: nwọn rubọ si Baalimu, nwọn si fi turari joná si ere fifin. 3 Mo kọ́ Efraimu pẹlu lati rìn, mo dì wọn mu li apa, ṣugbọn nwọn kò mọ̀ pe mo ti mu wọn lara dá. 4 Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo si ri si wọn bi awọn ti o mu ajàga kuro li ẹrẹkẹ wọn, mo si gbe onjẹ kalẹ niwaju wọn. 5 On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà. 6 Idà yio si ma gbe inu ilu rẹ̀, yio si run ìtikun rẹ̀, yio si jẹ wọn run, nitori ìmọran ara wọn. 7 Awọn enia mi si tẹ̀ si ifàsẹhin kuro lọdọ mi: bi o tilẹ̀ ṣepe nwọn pè wọn si Ọga-ogo jùlọ, nwọn kò jùmọ gbe e ga. 8 Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ, Efraimu? emi o ha ṣe gbà ọ silẹ, Israeli? emi o ha ti ṣe ṣe ọ bi Adma? emi o ha ti ṣe gbe ọ kalẹ bi Seboimu, ọkàn mi yi ninu mi, iyọnu mi gbiná pọ̀. 9 Emi kì yio mu gbigboná ibinu mi ṣẹ, emi kì yio yipadà lati run Efraimu: nitori Ọlọrun li emi, kì iṣe enia; Ẹni-Mimọ lãrin rẹ: emi kì yio si wá ninu ibinu. 10 Nwọn o ma tẹ̀le Oluwa: on o ke ramùramù bi kiniun: nigbati on o ke, nigbana li awọn ọmọ yio wariri lati iwọ-õrun wá. 11 Nwọn o warìri bi ẹiyẹ lati Egipti wá, ati bi adàba lati ilẹ Assiria wá: emi o si fi wọn si ile wọn, li Oluwa wi.

Ìdájọ́ lórí Juda ati Israẹli

12 Efraimu fi eke sagbàra yi mi ka, ile Israeli si fi ẹtàn sagbàra yi mi ka: ṣugbọn Juda njọba sibẹ̀ pẹlu Ọlọrun, o si ṣe olõtọ pẹlu Ẹni-mimọ́.

Hosea 12

1 EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti. 2 Oluwa ni ẹjọ kan ba Juda rò pẹlu, yio si jẹ Jakobu ni iyà gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀; gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ ni yio san padà fun u. 3 O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun. 4 Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ; 5 Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀. 6 Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.

Àwọn Ìdájọ́ Mìíràn

7 Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara. 8 Efraimu si wipe, Ṣugbọn emi di ọlọrọ̀, mo ti ri ini fun ara mi: ninu gbogbo lãlã mi nwọn kì yio ri aiṣedẽde kan ti iṣe ẹ̀ṣẹ lara mi. 9 Ati emi, Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ̀ Egipti wá, yio si tún mu ọ gbe inu agọ, bi ọjọ ajọ-ọ̀wọ wọnni. 10 Emi ti sọ̀rọ nipa awọn woli pẹlu, mo si ti mu iran di pupọ̀, mo ti ṣe ọ̀pọlọpọ akàwe, nipa ọwọ́ awọn woli. 11 Aiṣedẽde mbẹ ni Gileadi bi? nitõtọ asan ni nwọn: nwọn rubọ akọ malu ni Gilgali; nitõtọ, pẹpẹ wọn dabi ebè ni aporo oko. 12 Jakobu si salọ si ilẹ Siria: Israeli si sìn nitori aya kan; ati nitori aya kan li o ṣọ agùtan. 13 Ati nipa woli kan ni Oluwa mu Israeli jade ni Egipti: nipa woli kan li a si pa on mọ. 14 Efraimu mu u binu kikorò: nitorina ni yio fi ẹjẹ̀ rẹ̀ si ori rẹ̀, ẹgàn rẹ̀ li Oluwa rẹ̀ yio si san padà fun u.

Hosea 13

Paríparí Ìdájọ́ Israẹli

1 NIGBATI Efraimu sọ̀rọ, ìwarìri ni; o gbe ara rẹ̀ ga ni Israeli; ṣugbọn nigbati o ṣẹ̀ ninu Baali, o kú. 2 Nisisiyi, nwọn si dá ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ, nwọn si ti fi fàdakà wọn ṣe ere didà fun ara wọn, ati òriṣa ìmọ wọn: iṣẹ oniṣọnà ni gbogbo rẹ̀; nwọn wi niti wọn pe, Jẹ ki awọn enia ti nrubọ fi ẹnu kò awọn ọmọ malu li ẹnu. 3 Nitorina ni nwọn o ṣe dabi kũkũ owurọ̀, ati bi irì owurọ̀ ti nkọja lọ, bi iyangbò ti a ti ọwọ́ ijì gbá kuro ninu ilẹ ipakà, ati bi ẹ̃fin ti ijade kuro ninu ile ẹ̃fin. 4 Ṣugbọn emi li Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ Egipti wá, iwọ kì yio si mọ̀ ọlọrun kan bikòṣe emi: nitori kò si olugbàla kan lẹhìn mi. 5 Emi ti mọ̀ ọ li aginjù, ni ilẹ ti o pongbẹ. 6 Gẹgẹ bi a ti bọ́ wọn, bẹ̃ni nwọn yó; nwọn yó, nwọn si gbe ọkàn wọn ga; nitorina ni nwọn ṣe gbagbe mi. 7 Nitorina li emi o ṣe dabi kiniun si wọn; emi o si ma ṣọ wọn bi ẹkùn li ẹ̀ba ọ̀na. 8 Emi o pade wọn bi beari ti a gbà li ọ̀mọ, emi o si fà àwọn ọkàn wọn ya, nibẹ̀ ni emi o si jẹ wọn run bi kiniun, ẹranko igbẹ ni yio fà wọn ya. 9 Israeli, iwọ ti pa ara rẹ run, niti pe iwọ wà lodi si emi, irànlọwọ rẹ. 10 Nibo li ọba rẹ gbe wà nisisiyi ninu gbogbo ilu rẹ, ti o le gbà ọ? ati awọn onidajọ rẹ, niti awọn ti iwọ wipe; Fun mi li ọba ati awọn ọmọ-alade. 11 Emi fun ọ li ọba ni ibinu mi, mo si mu u kuro ni irúnu mi. 12 A dì aiṣedẽde Efraimu; ẹ̀ṣẹ rẹ̀ pamọ. 13 Irora obinrin ti nrọbi yio de si i: alaigbọn ọmọ li on; nitori on kò duro li akokò si ibi ijade ọmọ. 14 Emi o rà wọn padà lọwọ agbara isà-okú; Emi o rà wọn padà lọwọ ikú; Ikú, ajàkalẹ arùn rẹ dà? Isà-okú, iparun rẹ dà? ironupiwàda yio pamọ kuro loju mi. 15 Bi on tilẹ ṣe eleso ninu awọn arakunrin rẹ̀, afẹfẹ́ ilà-õrùn kan yio de, afẹ̃fẹ́ Oluwa yio ti aginjù wá, orisun rẹ̀ yio si gbẹ, ati oju isun rẹ̀ li a o mu gbẹ: on o bà ohun elò daradara gbogbo jẹ. 16 Samaria yio di ahoro: nitoriti on ti ṣọ̀tẹ si Ọlọrun rẹ̀: nwọn o ti ipa idà ṣubu: a o fọ́ ọmọ wọn tũtũ, ati aboyún wọn li a o là ni inu.

Hosea 14

Ẹ̀bẹ̀ Hosea fún Israẹli

1 ISRAELI, yipadà si Oluwa Ọlọrun rẹ, nitori iwọ ti ṣubu ninu aiṣedẽde rẹ. 2 Mu ọ̀rọ pẹlu nyin, ẹ si yipadà si Oluwa: ẹ wi fun u pe, Mu aiṣedẽde gbogbo kuro, si fi ore-ọfẹ gbà wa: bẹ̃ni awa o fi ọmọ malu ète wa san a fun ọ. 3 Assuru kì yio gbà wa; awa kì yio gùn ẹṣin: bẹ̃ni awa kì yio tun wi mọ fun iṣẹ ọwọ́ wa pe, Ẹnyin li ọlọrun wa: nitori lọdọ rẹ ni alainibaba gbe ri ãnu.

OLUWA Ṣèlérí Ìgbé-Ayé Titun fún Israẹli

4 Emi o wo ifàsẹhìn wọn sàn, emi o fẹ wọn lọfẹ: nitori ibinu mi yí kuro lọdọ rẹ̀. 5 Emi o dabi ìri si Israeli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rẹ̀ bi Lebanoni. 6 Ẹka rẹ̀ yio tàn, ẹwà rẹ̀ yio si dabi igi olifi, ati õrùn rẹ̀ bi Lebanoni. 7 Awọn ti o ngbe abẹ ojiji rẹ̀ yio padà wá; nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara: õrun rẹ̀ yio dabi ọti-waini ti Lebanoni. 8 Efraimu yio wipe, Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ? Emi ti gbọ́, mo si ti kiyesi i: emi dabi igi firi tutù. Lati ọdọ mi li a ti ri èso rẹ.

Ọ̀rọ̀ Ìparí

9 Tali o gbọ́n, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ̀ wọn? nitori ọ̀na Oluwa tọ́, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.

Joeli 1

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Joeli ọmọ Petueli wá.

Ìdárò Nítorí Ìparun Nǹkan Ọ̀gbìn

2 Gbọ́ eyi, ẹnyin arugbo, si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ na. Eyi ha wà li ọjọ nyin, tabi li ọjọ awọn baba nyin? 3 Ẹ sọ ọ fun awọn ọmọ nyin, ati awọn ọmọ nyin fun awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ wọn fun iran miràn. 4 Eyi ti iru kòkoro kan jẹ kù ni ẽṣú jẹ; ati eyi ti ẽṣú jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ; eyiti kòkoro na si jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ. 5 Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin. 6 Nitori orilẹ-ède kan goke wá si ilẹ mi, o li agbara, kò si ni iye, ehin ẹniti iṣe ehin kiniun, o si ni erìgi abo kiniun. 7 O ti pa àjara mi run, o si ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọtọ́ mi kuro, o ti bó o jalẹ, o si sọ ọ nù; awọn ẹ̀ka rẹ̀ li a si sọ di funfun. 8 Ẹ pohùnrére-ẹkun bi wundia ti a fi aṣọ ọ̀fọ dì li àmure, nitori ọkọ igbà ewe rẹ̀. 9 A ké ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu kuro ni ile Oluwa; awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, ṣọ̀fọ. 10 Oko di ìgboro, ilẹ nṣọ̀fọ, nitori a fi ọkà ṣòfo: ọti-waini titun gbẹ, ororo mbuṣe. 11 Ki oju ki o tì nyin, ẹnyin agbẹ̀; ẹ hu, ẹnyin olùtọju àjara, nitori alikamà ati nitori ọkà barli; nitori ikorè oko ṣègbe. 12 Ajara gbẹ, igi ọ̀pọtọ́ si rọgbẹ; igi pomegranate, igi ọ̀pẹ pẹlu, ati igi appili, gbogbo igi igbo li o rọ: nitoriti ayọ̀ rọgbẹ kuro lọdọ awọn ọmọ enia. 13 Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin. 14 Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa, 15 A! fun ọjọ na, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ, ati bi iparun lati ọwọ́ Olodumare ni yio de. 16 A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa? 17 Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ. 18 Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro. 19 Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ. 20 Awọn ẹranko igbẹ gbé oju soke si ọ pẹlu: nitoriti awọn iṣàn omi gbẹ, iná si ti jó awọn pápa oko aginju run.

Joeli 2

Ọ̀wọ́ Eeṣú, gẹ́gẹ́ bí Àmì Ìkéde Ọjọ́ OLUWA

1 Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ si dá idagìri ni oke mimọ́ mi; jẹ ki awọn ará ilẹ na warìri: nitoriti ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, nitori o kù si dẹ̀dẹ; 2 Ọjọ òkunkun ati òkudu, ọjọ ikũku ati òkunkun biribiri, bi ọyẹ̀ owurọ̀ ti ilà bò ori awọn oke-nla: enia nla ati alagbara; kò ti isi iru rẹ̀ ri, bẹ̃ni iru rẹ̀ kì yio si mọ lẹhin rẹ̀, titi de ọdun iran de iran. 3 Iná njó niwaju wọn; ọwọ́-iná si njó lẹhin wọn: ilẹ na dàbi ọgbà Edeni niwaju wọn, ati lẹhin wọn bi ahoro ijù; nitõtọ, kò si si ohun ti yio bọ́ lọwọ wọn. 4 Irí wọn dàbi irí awọn ẹṣin; ati bi awọn ẹlẹṣin, bẹ̃ni nwọn o sure. 5 Bi ariwo kẹkẹ́ lori oke ni nwọn o fò, bi ariwo ọwọ́-iná ti o jó koriko gbigbẹ, bi alagbara enia ti a tẹ́ ni itẹ́gun. 6 Li oju wọn, awọn enia yio jẹ irora pupọ̀: gbogbo oju ni yio ṣú dùdu. 7 Nwọn o sare bi awọn alagbara; nwọn o gùn odi bi ọkunrin ologun; olukuluku wọn o si rìn lọ li ọ̀na rẹ̀, nwọn kì yio si bà ọ̀wọ́ wọn jẹ. 8 Bẹ̃ni ẹnikan kì yio tì ẹnikeji rẹ̀; olukuluku wọn o rìn li ọ̀na rẹ̀: nigbati nwọn ba si ṣubu lù idà, nwọn kì o gbọgbẹ́. 9 Nwọn o sure siwa sẹhin ni ilu: nwọn o sure lori odi, nwọn o gùn ori ile; nwọn o gbà oju fèrese wọ̀ inu ile bi olè. 10 Aiye yio mì niwaju wọn; awọn ọrun yio warìri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhìn. 11 Oluwa yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ jade niwaju ogun rẹ̀: nitori ibùdo rẹ̀ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nitori ọjọ Oluwa tobi o si li ẹ̀ru gidigidi; ara tali o le gbà a?

Ìpè fún Ìrònúpìwàdà

12 Njẹ nitorina nisisiyi, ni Oluwa wi, Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu ãwẹ̀, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu ọ̀fọ. 13 Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu. 14 Tali o mọ̀ bi on o yipadà, ki o si ronupiwàda, ki o si fi ibukún silẹ̀ lẹhin rẹ̀; ani ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu fun Oluwa Ọlọrun nyin? 15 Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ yà ãwẹ̀ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ ti o ni irònu. 16 Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀. 17 Jẹ ki awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, sọkun lãrin iloro ati pẹpẹ, si jẹ ki wọn wi pe, Dá awọn enia rẹ si, Oluwa, má si ṣe fi iní rẹ fun ẹ̀gan, ti awọn keferi yio fi ma jọba lori wọn: ẽṣe ti nwọn o fi wi ninu awọn enia pe, Ọlọrun wọn há da?

Ọlọrun Yóo Dá Ìbísí Pada sórí Ilẹ̀ náà

18 Nigbana ni Oluwa yio jowú fun ilẹ rẹ̀, yio si kãnu fun enia rẹ̀. 19 Nitõtọ, Oluwa yio dahùn, yio si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, Wò o emi o rán ọkà, ati ọti-waini, ati ororo si nyin, a o si fi wọn tẹ́ nyin lọrùn: emi kì yio si fi nyin ṣe ẹ̀gan mọ lãrin awọn keferi. 20 Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla. 21 Má bẹ̀ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ̀: nitori Oluwa yio ṣe ohun nla. 22 Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn. 23 Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ̀ ninu Oluwa Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ̀ ojò fun nyin bi o ti tọ́, on o si mu ki ojò rọ̀ silẹ fun nyin, akọrọ̀ ati arọ̀kuro ojò ni oṣù ikini. 24 Ati awọn ilẹ ipakà yio kún fun ọkà, ati ọpọ́n wọnni yio ṣàn jade pẹlu ọti-waini ati ororo. 25 Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin. 26 Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai. 27 Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi wà lãrin Israeli, ati pe: Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, kì iṣe ẹlomiràn: oju kì yio si tì awọn enia mi lai.

Ọjọ́ OLUWA

28 Yio si ṣe, nikẹhìn emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo; ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma ṣotẹlẹ, awọn arugbo nyin yio ma lá alá, awọn ọdọmọkunrin nyin yio ma riran: 29 Ati pẹlu si ara awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin, ati si ara awọn ọmọ-ọdọ obinrin, li emi o tú ẹmi mi jade li ọjọ wọnni. 30 Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn li ọrun ati li aiye, ẹjẹ̀ ati iná, ati ọwọ̀n ẹ̃fin. 31 A ó sọ õrùn di òkunkun, ati oṣùpá di ẹjẹ̀, ki ọjọ nla ati ẹ̀ru Oluwa to de. 32 Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè.

Joeli 3

OLUWA Yóo Ṣe Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 NITORINA kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalemu padà bọ̀. 2 Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi. 3 Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu. 4 Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin. 5 Nitoriti ẹnyin ti mu fàdakà mi ati wurà mi, ẹnyin si ti mu ohun rere daradara mi lọ sinu tempili nyin: 6 Ati awọn ọmọ Juda, ati awọn ọmọ Jerusalemu li ẹnyin ti tà fun awọn ara Griki, ki ẹnyin ba le sìn wọn jina kuro li agbègbe wọn. 7 Kiyesi i, emi o gbe wọn dide kuro nibiti ẹnyin ti tà wọn si, emi o si san ẹsan nyin padà sori ara nyin. 8 Emi o si tà awọn ọmọkunrin nyin ati awọn ọmọbinrin nyin si ọwọ́ awọn ọmọ Juda, nwọn o si tà wọn fun awọn ara Sabia, fun orilẹ-ède kan ti o jinà rére, nitori Oluwa li o ti sọ ọ. 9 Ẹ kede eyi li ãrin awọn keferi; ẹ yà ogun si mimọ́, ẹ ji awọn alagbara, ẹ sunmọ tòsi, ẹ goke wá gbogbo ẹnyin ọkunrin ologun. 10 Ẹ fi irin ọkọ́ itulẹ̀ nyin rọ idà, ati dojé nyin rọ ọkọ̀: jẹ ki alailera wi pe, Ara mi le koko. 11 Ẹ kó ara nyin jọ, si wá, gbogbo ẹnyin keferi, ẹ si gbá ara nyin jọ yikakiri: nibẹ̀ ni ki o mu awọn alagbara rẹ sọkalẹ, Oluwa. 12 Ẹ ji, ẹ si goke wá si afonifojì Jehoṣafati ẹnyin keferi: nitori nibẹ̀ li emi o joko lati ṣe idajọ awọn keferi yikakiri. 13 Ẹ tẹ̀ doje bọ̀ ọ, nitori ikore pọ́n: ẹ wá, ẹ sọkalẹ; nitori ifunti kún, nitori awọn ọpọ́n kún rekọja, nitori ìwa-buburu wọn pọ̀. 14 Ọ̀pọlọpọ, ọ̀pọlọpọ li afonifojì idajọ, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ ni afonifojì idajọ. 15 Õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, ati awọn irawọ̀ yio fà titàn wọn sẹhin.

Ọlọrun Yóo Bukun Àwọn Eniyan Rẹ̀

16 Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli. 17 Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ. 18 Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu. 19 Egipti yio di ahoro, Edomu yio si di aginju ahoro, nitori ìwa ipá si awọn ọmọ Juda, nitoriti nwọn ti ta ẹjẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ ni ilẹ wọn. 20 Ṣugbọn Juda yio joko titi lai, ati Jerusalemu lati iran de iran. 21 Nitori emi o wẹ̀ ẹjẹ̀ wọn nù, ti emi kò ti wẹ̀nu: nitori Oluwa ngbe Sioni.

Amosi 1

1 Ọ̀RỌ Amosi, ẹniti o wà ninu awọn darandaran Tekoa, ti o ri niti Israeli li ọjọ ọba Ussiah ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli, ọdun meji ṣãju isẹ̀lẹ nì. 2 O si wipe, Oluwa yio bu jade lati Sioni wá, yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ lati Jerusalemu wá; ibùgbe awọn olùṣọ-agùtan yio si ṣọ̀fọ, oke Karmeli yio si rọ.

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Ó yí Israẹli ká Siria

3 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti fi ohunèlo irin ipakà pa Gileadi: 4 Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run. 5 Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi.

Filistia

6 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti kó gbogbo igbèkun ni igbèkun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ. 7 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run: 8 Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi.

Tire

9 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Tire, ati nitori mẹrin: emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn fi gbogbo igbèkun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin. 10 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run. 11 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si gbe gbogbo ãnu sọnù; ibinu rẹ̀ si nfaniya titi, o si pa ibinu rẹ̀ mọ titi lai. 12 Ṣugbọn emi o rán iná kan si Temani, ti yio jó afin Bosra wọnni run.

Amoni

13 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti là inu awọn aboyun Gileadi, ki nwọn le ba mu agbègbe wọn tobi: 14 Ṣugbọn emi o da iná kan ninu odi Rabba, yio si jó ãfin rẹ̀ wọnni run, pẹlu iho ayọ̀ li ọjọ ogun, pẹlu ijì li ọjọ ãjà: 15 Ọba wọn o si lọ si igbèkun, on ati awọn ọmọ-alade rẹ̀ pọ̀, li Oluwa wi.

Amosi 2

Moabu

1 BAYI li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o ti sun egungun ọba Edomu di ẽrú. 2 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Moabu, yio si jó ãfin Kirioti wọnni run: Moabu yio si kú pẹlu ariwo, pẹlu iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè: 3 Emi o si ké onidajọ kurò lãrin rẹ̀, emi o si pa gbogbo ọmọ-alade inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀; li Oluwa wi.

Juda

4 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa aṣẹ rẹ̀ mọ, eke wọn si ti mu wọn ṣina, eyiti awọn baba wọn ti tẹ̀le. 5 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Juda, yio si jó ãfin Jerusalemu wọnni run.

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Israẹli

6 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji; 7 Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ. 8 Nwọn si dùbulẹ le aṣọ ti a fi lelẹ fun ògo lẹba olukuluku pẹpẹ, nwọn si mu ọti-waini awọn ti a yá, ni ile ọlọrun wọn. 9 Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá. 10 Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori. 11 Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. 12 Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasarite ni ọti-waini mu, ẹ si paṣẹ fun awọn woli pe, Ẹ máṣe sọtẹlẹ. 13 Wò o, emi o tẹ̀ nyin mọlẹ, bi kẹkẹ́ ti o kún fun ití ti itẹ̀. 14 Nitorina sisá yio dẹti fun ẹni yiyara, onipá kì yio si mu ipa rẹ̀ le, bẹ̃ni alagbara kì yio le gba ara rẹ̀ là. 15 Bẹ̃ni tafàtafà kì yio duro; ati ẹniti o yasẹ̀ kì yio le gbà ara rẹ̀ là: bẹ̃ni ẹniti ngùn ẹṣin kì yio gbà ara rẹ̀ là: 16 Ati ẹniti o gboiyà ninu awọn alagbara yio salọ ni ihòho li ọjọ na, li Oluwa wi.

Amosi 3

1 Ẹ gbọ̀ ọ̀rọ yi ti Oluwa ti sọ si nyin, ẹnyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mú goke lati ilẹ Egipti wá, wipe, 2 Ẹnyin nikan ni mo mọ̀ ninu gbogbo idile aiye: nitorina emi o bẹ̀ nyin wò nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin.

Iṣẹ́ Wolii

3 Ẹni meji lè rìn pọ̀, bikòṣepe nwọn rẹ́? 4 Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu? 5 Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara? 6 A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e? 7 Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀. 8 Kiniun ti ké ramùramù, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ̀rọ, tani lè ṣe aisọtẹlẹ?

Ìparun Samaria

9 Ẹ kede li ãfin Aṣdodu, ati li ãfin ni ilẹ Egipti, ki ẹ si wipe, Pè ara nyin jọ lori awọn oke nla Samaria, ki ẹ si wò irọkẹ̀kẹ nla lãrin rẹ̀, ati inilara lãrin rẹ̀. 10 Nitori nwọn kò mọ̀ bi ati ṣe otitọ, li Oluwa wi, nwọn ti kó ìwa-ipá ati ìwa-olè jọ li ãfin wọn. 11 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ọta kan yio si wà yi ilẹ na ka; on o si sọ agbara rẹ kalẹ kuro lara rẹ, a o si kó ãfin rẹ wọnni. 12 Bayi li Oluwa wi; gẹgẹ bi oluṣọ-agùtan iti gbà itan meji kuro li ẹnu kiniun, tabi ẹlà eti kan; bẹ̃li a o mu awọn ọmọ Israeli ti ngbe Samaria kuro ni igun akete, ati ni aṣọ Damasku irọ̀gbọku. 13 Ẹ gbọ́, ẹ si jẹri si ile Jakobu, li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, 14 Pe, li ọjọ ti emi o bẹ̀ irekọja Israeli wò lara rẹ̀, emi o bẹ̀ awọn pẹpẹ Beteli wò pẹlu: a o si ké iwo pẹpẹ kuro, nwọn o si wó lulẹ. 15 Emi o si lù ile otutù pẹlu ile ẹ̃rùn; ile ehín erin yio si ṣègbe, ile nla wọnni yio si li opin, li Oluwa wi.

Amosi 4

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi, ẹnyin ọmọ malu Baṣan, ti o wà li oke nla Samaria, ti o nni talakà lara, ti o ntẹ̀ alaini rẹ́, ti o nwi fun oluwa wọn pe, Gbe wá, ki a si mu. 2 Oluwa Ọlọrun ti bura ninu iwà-mimọ́ rẹ̀, pe, Sa wò o, ọjọ wọnni yio de ba nyin, ti on o fi ìwọ gbe nyin kuro, yio si fi ìwọ-ẹja gbe iran nyin. 3 Ati ni ibi yiya odi wọnni li ẹnyin o ba jade lọ, olukuluku niwaju rẹ̀ gan; ẹnyin o si gbe ara nyin sọ si Harmona, li Oluwa wi.

Israẹli Kọ̀, Kò kẹ́kọ̀ọ́

4 Ẹ wá si Beteli, ki ẹ si dẹṣẹ: ẹ mu irekọja nyin pọ̀ si i ni Gilgali; ẹ si mu ẹbọ nyin wá li orowurọ̀, ati idamẹwa nyin lẹhìn ọdun mẹta. 5 Ki ẹ si ru ẹbọ ọpẹ́ pẹlu iwukara, ẹ kede, ki ẹ si fi ọrẹ atinuwa lọ̀: nitori bẹ̃li ẹnyin fẹ́, ẹnyin ọmọ Israeli, li Oluwa Ọlọrun wi. 6 Emi pẹlu si ti fun nyin ni mimọ́ ehín ni gbogbo ilu nyin, ati aini onjẹ, ni ibùgbe nyin gbogbo: sibẹ̀ ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. 7 Ati pẹlu, emi ti fà ọwọ́ òjo sẹhìn kuro lọdọ nyin, nigbati o kù oṣù mẹta si i fun ikorè; emi si ti mu òjo rọ̀ si ilu kan, emi kò si jẹ ki o rọ̀ si ilu miràn: o rọ̀ si apakan, ibiti kò gbe rọ̀ si si rọ. 8 Bẹ̃ni ilu meji tabi mẹta nrìn lọ si ilu kan, lati mu omi: ṣugbọn kò tẹ́ wọn lọrùn: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. 9 Mo ti fi irẹ̀danù ati imúwòdú lù nyin: nigbati ọgbà nyin ati ọgbà-àjara nyin, ati igi ọ̀pọtọ́ nyin, ati igi olifi nyin npọ̀ si i, kòkoro jẹ wọn run; sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. 10 Mo ti rán ajàkalẹ-arùn si ãrin nyin, gẹgẹ bi ti Egipti: awọn ọdọmọkunrin nyin li emi si ti fi idà pa, nwọn si ti kó ẹṣin nyin ni igbèkun pẹlu; mo si ti jẹ ki õrùn ibùdo nyin bù soke wá si imú nyin: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. 11 Mo ti bì ṣubu ninu nyin, bi Ọlọrun ti bì Sodomu on Gomorra ṣubu, ẹnyin si dàbi oguná ti a fà yọ kuro ninu ijoná: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. 12 Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israeli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israeli. 13 Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

Amosi 5

Ìpè sí Ìrònúpìwàdà

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi ti emi gbe soke si nyin, ani ohùnrére ẹkun, ẹnyin ile Israeli. 2 Wundia Israeli ti ṣubu; kì yio dide mọ: a kọ̀ ọ silẹ lori ilẹ rẹ̀; kò si ẹniti yio gbe e dide. 3 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ilu ti o jade lọ li ẹgbẹrun yio ṣikù ọgọrun; eyiti o si jade lọ li ọgọrun yio ṣikù mẹwa, fun ile Israeli. 4 Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Israeli, ẹ wá mi, ẹnyin o si yè: 5 Ṣugbọn ẹ máṣe wá Beteli, bẹ̃ni ki ẹ má wọ̀ inu Gilgali lọ, ẹ má si rekọja lọ si Beerṣeba: nitori lõtọ Gilgali yio lọ si igbèkun, Beteli yio si di asan. 6 Ẹ wá Oluwa, ẹnyin o si yè; ki o má ba gbilẹ bi iná ni ile Josefu, a si jó o run, ti kì o fi si ẹnikan lati pá a ni Beteli. 7 Ẹnyin ti ẹ sọ idajọ di iwọ, ti ẹ si kọ̀ ododo silẹ li aiye. 8 Ẹ wá ẹniti o dá irawọ̀ meje nì ati Orioni, ti o si sọ ojiji ikú di owurọ̀, ti o si fi oru mu ọjọ ṣokùnkun: ti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade soju aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀: 9 Ti o mu iparun kọ manà sori alagbara, tobẹ̃ ti iparun yio wá si odi agbara. 10 Nwọn korira ẹniti nbaniwi li ẹnu bodè, nwọn si korira ẹniti nsọ otitọ. 11 Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn. 12 Nitori mo mọ̀ onirũru irekọja nyin, ati ẹ̀ṣẹ nla nyin: nwọn npọ́n olododo loju, nwọn ngbà owo abẹ̀tẹlẹ, nwọn si nyi awọn talakà si apakan ni bodè, kuro ninu are wọn. 13 Nitorina ẹni-oye yio dakẹ nigbana; nitori akòko ibi ni. 14 Ẹ ma wá ire, kì isi iṣe ibi, ki ẹ ba le yè; bẹ̃ni Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, yio si pẹlu nyin, bi ẹnyin ti wi. 15 Ẹ korira ibi, ẹ si fẹ́ ire, ki ẹ si fi idajọ gunlẹ ni bodè; boya Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun yio ṣe ojurere si iyokù Josefu. 16 Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún. 17 Ati ni gbogbo ọ̀gba àjara ni isọkún yio gbe wà: nitori emi o kọja lãrin rẹ, li Oluwa wi. 18 Egbe ni fun ẹnyin ti ẹ nfẹ́ ọjọ Oluwa! kili eyi o jasi fun nyin? ọjọ Oluwa òkunkun ni, kì isi iṣe imọlẹ. 19 Gẹgẹ bi enia ti o sa fun kiniun, ti beari si pade rẹ̀; tabi ti o wọ̀ inu ile, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ tì lara ogiri, ti ejò si bù u jẹ. 20 Ọjọ Oluwa kì o ha ṣe òkunkun laiṣe imọlẹ? ani òkunkun biribiri, laisi imọlẹ ninu rẹ̀? 21 Mo korira, mo si kẹgàn ọjọ asè nyin, emi kì o si gbõrùn ọjọ ajọ ọ̀wọ nyin. 22 Bi ẹnyin tilẹ rú ẹbọ sisun ati ẹbọ jijẹ nyin si mi, emi kì o si gbà wọn: bẹ̃ni emi ki yio nani ẹbọ ọpẹ́ ẹran abọ́pa nyin. 23 Mu ariwo orin rẹ kuro lọdọ mi; nitori emi kì o gbọ́ iró adùn fioli rẹ. 24 Ṣugbọn jẹ ki idajọ ki o ṣàn silẹ bi omi, ati ododo bi iṣàn omi nla. 25 Ẹnyin ha ti rubọ si mi, ẹ ha ti ta mi lọrẹ li aginjù li ogoji ọdun, ẹnyin ile Israeli. 26 Ṣugbọn ẹnyin ti rù agọ Moloku ati Kiuni nyin, awọn ere nyin, irawọ̀ òriṣa nyin, ti ẹ ṣe fun ara nyin. 27 Nitorina, emi o mu ki ẹ lọ si igbèkun rekọja Damasku, li Oluwa wi, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

Amosi 6

Ìparun Israẹli

1 EGBE ni fun ẹniti ara rọ̀ ni Sioni, ati awọn ti o gbẹkẹ̀le oke nla Samaria, awọn ti a pè ni ikini ninu awọn orilẹ-ède, awọn ti ile Israeli tọ̀ wá! 2 Ẹ kọja si Kalne, si wò; ẹ si ti ibẹ̀ lọ si Hamati nla: lẹhìn na ẹ sọ̀kalẹ lọ si Gati ti awọn Filistini: nwọn ha san jù ilẹ ọba wọnyi lọ? tabi agbègbe wọn ha tobi jù agbègbe nyin lọ? 3 Ẹnyin ti o sún ọjọ ibi siwaju, ti ẹ si mu ibùgbe ìwa-ipá sunmọ tòsi; 4 Awọn ti o ndùbulẹ lori akete ehin-erin, ti nwọn si nnà ara wọn lori irọ̀gbọku wọn, ti nwọn njẹ ọdọ-agùtan inu agbo, ati ẹgbọ̀rọ malu inu agbo; 5 Ti nwáhùn si iró orin fioli, ti nwọn si nṣe ohun-ikọrin fun ara wọn, bi Dafidi; 6 Awọn ti nmuti ninu ọpọ́n waini, ti nwọn si nfi olori ororo kun ara wọn; ṣugbọn nwọn kò banujẹ nitori ipọnju Josefu. 7 Nitorina awọn ni o lọ si igbèkun pẹlu awọn ti o ti kọ́ lọ si igbèkun; àse awọn ti nṣe aṣeleke li a o mu kuro. 8 Oluwa Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ bura, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ ogun wi, Emi korira ọlanla Jakobu, mo si korira ãfin rẹ̀: nitorina li emi o ṣe fi ilu na, ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀ tọrẹ. 9 Yio si ṣe, bi enia mẹwa li o ba kù ninu ile kan, nwọn o si kú. 10 Ati arakunrin rẹ̀, ati ẹniti o nfi i joná, lati kó egungun wọnni jade kuro ninu ile, yio gbe e, yio si bi ẹniti o wà li ẹba ile lere pe, O ha tun kù ẹnikan pẹlu rẹ? On o si wipe, Bẹ̃kọ̀. Nigbana li on o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ: nitoripe awa kò gbọdọ da orukọ Oluwa. 11 Nitori kiyesi i, Oluwa paṣẹ, yio si fi iparun kọlù ile nla na, ati aisàn kọlù ile kékèké. 12 Ẹṣin ha le ma sure lori apata? ẹnikan ha le fi akọ malu ṣiṣẹ ìtulẹ̀ nibẹ̀? nitoriti ẹnyin ti yi idajọ dà si oró, ati eso ododo dà si iwọ: 13 Ẹnyin ti nyọ̀ si ohun asan, ti nwipe, Nipa agbara ara wa kọ́ li awa fi gbà iwo fun ara wa? 14 Ṣugbọn kiyesi i, emi o gbe orilẹ-ède kan dide si nyin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi; nwọn o si pọ́n nyin loju lati iwọle Hamati, titi de odò pẹ̀tẹlẹ.

Amosi 7

Ìran Nípa Eeṣú

1 BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi; si wò o, o dá ẽṣú ni ibẹ̀rẹ irú-soke idàgba ikẹhin, si wò o, idàgba ikẹhìn lẹhìn ike-kuro ti ọba nì. 2 O si ṣe, ti nwọn jẹ koriko ilẹ na tan, nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, darijì, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. 3 Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Kì yio ṣe, li Oluwa wi.

Ìran Nípa Iná

4 Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run. 5 Nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, dawọ duro, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. 6 Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Eyi pẹlu kì yio ṣe, li Oluwa Ọlọrun wi.

Ìran Nípa Okùn Ìwọ̀n Àwọn Mọlémọlé

7 Bayi li on fi hàn mi: si wò o, Oluwa duro lori odi kan, ti a fi okùn-ìwọn ti o run mọ, ti on ti okùn-ìwọn ti o run li ọwọ́ rẹ̀. 8 Oluwa si wi fun mi pe, Amosi, kini iwọ ri? Emi si wipe, Okùn-ìwọn kan ti o run ni. Nigbana ni Oluwa wipe, Wò o, emi o fi okùn-ìwọn rirun kan le ilẹ lãrin Israeli enia mi: emi kì yio si tun kọja lọdọ wọn mọ: 9 Ibi giga Israeli wọnni yio si di ahoro: ati ibi mimọ́ Israeli wọnni yio di ahoro; emi o si fi idà dide si ile Jeroboamu.

Amosi ati Amasiah

10 Nigbana ni Amasiah, alufa Beteli ranṣẹ si Jeroboamu ọba Israeli, wipe, Amosi ti ditẹ̀ si ọ lãrin ile Israeli: ilẹ kò si le gba gbogbo ọ̀rọ rẹ̀. 11 Nitori bayi li Amosi wi, Jeroboamu yio ti ipa idà kú, nitõtọ Israeli li a o si fà lọ si igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀. 12 Amasiah sọ fun Amosi pẹlu pe, Iwọ ariran, lọ, salọ si ilẹ Juda, si ma jẹun nibẹ̀, si ma sọtẹlẹ nibẹ̀: 13 Ṣugbọn máṣe sọtẹlẹ̀ mọ ni Beteli: nitori ibi mimọ́ ọba ni, ãfin ọba si ni. 14 Nigbana ni Amosi dahùn, o si wi fun Amasiah pe, Emi ki iṣe woli ri, bẹ̃ni emi kì iṣe ọmọ woli, ṣugbọn olùṣọ-agùtan li emi ti iṣe ri, ati ẹniti iti ma ká eso ọpọ̀tọ: 15 Oluwa si mu mi, bi mo ti ntọ̀ agbo-ẹran lẹhìn, Oluwa si wi fun mi pe, Lọ, sọtẹlẹ̀ fun Israeli enia mi. 16 Njẹ nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Iwọ wipe, Máṣe sọtẹlẹ̀ si Israeli, má si jẹ ki ọ̀rọ rẹ kán silẹ si ile Isaaki. 17 Nitorina bayi li Oluwa wi; Obinrin rẹ yio di panṣagà ni ilu, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, yio ti ipa idà ṣubu; ilẹ rẹ li a o si fi okùn pin; iwọ o si kú ni ilẹ aimọ́: nitõtọ, a o si kó Israeli lọ ni igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀.

Amosi 8

Ìran Nípa Agbọ̀n Èso

1 BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si kiyesi i, agbọ̀n eso ẹrùn kan. 2 On si wipe, Amosi, kili ohun ti iwọ ri? Emi si wipe, Agbọ̀n eso ẹrùn ni. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Opin de si Israeli enia mi; emi kì yio tún kọja lọdọ wọn mọ. 3 Orin inu tempeli yio si jẹ hihu li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi: okú pupọ̀ ni yio wà ni ibi gbogbo; nwọn o ma fi idakẹ jù wọn sode.

Ìparun Israẹli

4 Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin ti ngbe awọn alaini mì, lati sọ awọn talakà ilẹ na di alaini, 5 Ti nwipe, Nigbawo ni oṣù titún yio pari, ki awa ba le ta ọkà? ati ọjọ isimi, ki awa ba le ṣi alikama silẹ, ki a si ṣe ìwọn efà kere, ati ìwọn ṣekeli tobi, ki a si ma fi ẹ̀tan yi ìwọn padà? 6 Ki awa le fi fàdakà rà talakà, ati bàta ẹsẹ̀ mejeji rà alaini, ki a si tà eyiti o dànu ninu alikama? 7 Oluwa ti bura nipa ọlanla Jakobu pe, Nitõtọ emi kì yio gbàgbe ọkan ninu iṣẹ wọn. 8 Ilẹ na kì yio ha warìri nitori eyi, ati olukuluku ẹniti o ngbe inu rẹ̀ kì yio ha ṣọ̀fọ? yio si rú soke patapata bi kikún omi; a o si tì i jade, a o si tẹ̀ ẹ rì, gẹgẹ bi odò Egipti. 9 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si mu ki õrùn ki o wọ̀ lọsan, emi o si mu aiye ṣu òkunkun li ọ̀san gangan: 10 Emi o si yi àse nyin padà si ọ̀fọ, ati orin nyin gbogbo si ohùn-rére ẹkún: emi o si mu aṣọ ọ̀fọ wá si ẹgbẹ̀ gbogbo, ati pipá ori, si gbogbo ori; emi o si ṣe e ki o dàbi iṣọ̀fọ fun ọmọ kanṣoṣo ti a bi; ati opin rẹ̀ bi ọjọ kikorò. 11 Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, kì iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ́ ọ̀rọ Oluwa: 12 Nwọn o si ma rìn kiri lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de ila-õrun, nwọn o sare siwá sẹhìn lati wá ọ̀rọ Oluwa, nwọn kì yio si ri i. 13 Li ọjọ na li awọn arẹwà wundia, ati awọn ọdọmọkunrin yio daku fun ongbẹ. 14 Awọn ti o fi ẹ̀ṣẹ Samaria bura, ti nwọn si wipe, Iwọ Dani, ọlọrun rẹ mbẹ lãyè! ati ọ̀na Beerṣeba mbẹ lãyè! ani nwọn o ṣubu, nwọn kì yio si tún dide mọ.

Amosi 9

Ìdájọ́ OLUWA

1 MO ri Oluwa o duro lori pẹpẹ: o si wipe, Lù itẹrigbà ilẹ̀kun, ki awọn òpo ki o le mì: si ṣá wọn li ori, gbogbo wọn; emi o si fi idà pa ẹni ikẹhìn wọn: ẹniti o sá ninu wọn, kì yio salọ gbe; ati ẹniti o sa asalà ninu wọn li a kì yio gbàla. 2 Bi nwọn tilẹ wà ilẹ lọ si ọrun-apadi, lati ibẹ̀ li ọwọ́ mi yio ti tẹ̀ wọn; bi nwọn tilẹ gùn okè ọrun lọ; lati ibẹ̀ li emi o ti mu wọn sọ̀kalẹ: 3 Ati bi nwọn tilẹ fi ara wọn pamọ li ori oke Karmeli; emi o wá wọn ri, emi o si mu wọn kuro nibẹ̀; ati bi a tilẹ fi wọn pamọ kuro niwaju mi ni isàlẹ okun; lati ibẹ̀ na li emi o ti paṣẹ fun ejò nì, on o si bù wọn jẹ: 4 Ati bi nwọn tilẹ lọ si igbèkun niwaju awọn ọta wọn, lati ibẹ̀ wá li emi o ti paṣẹ fun idà, on o si pa wọn: emi a si tẹ̀ oju mi mọ wọn lara fun ibi, kì isi ṣe fun ire. 5 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li ẹniti o si fi ọwọ́ kan ilẹ na, yio si di yiyọ́, gbogbo awọn ti o ngbe inu rẹ̀ yio si ṣọ̀fọ: yio si rú soke patapata bi kikun omi: a o si tẹ̀ ẹ ri, bi odò Egipti. 6 On li ẹniti o kọ́ itẹ́ rẹ̀ ninu awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ ni ilẹ aiye: ẹniti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade si ori ilẹ aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀. 7 Ẹnyin kò ha dàbi awọn ọmọ Etiopia si mi, Ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Emi kò ha ti mu Israeli goke ti ilẹ Egipti jade wá? ati awọn Filistini lati ilẹ Kaftori, ati awọn ara Siria lati Kiri. 8 Kiyesi i, Oluwa Ọlọrun mbẹ lara ilẹ ọba ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, emi o si pa a run kuro lori ilẹ; ṣugbọn emi kì yio pa ile Jakobu run tan patapata, li Oluwa wi. 9 Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ. 10 Gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ninu enia mi yio ti ipa idà kú, ti nwipe, Ibi na kì yio le wa ba, bẹ̃ni kì yio ba wa lojijì.

Dídá Israẹli Pada Sípò Lọ́jọ́ Iwájú

11 Li ọjọ na li emi o gbe agọ Dafidi ti o ṣubu ró, emi o si dí ẹya rẹ̀; emi o si gbe ahoro rẹ̀ soke, emi o si kọ́ ọ bi ti ọjọ igbani: 12 Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni iní, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li Oluwa ti o nṣe eyi wi. 13 Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́. 14 Emi o si tun mu igbèkun Israeli enia mi padà bọ̀, nwọn o si kọ́ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn. 15 Emi o si gbìn wọn si ori ilẹ wọn, a kì yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li Oluwa Ọlọrun rẹ wi.

Obadiah 1

1 IRAN ti Obadiah. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti Edomu; Awa ti gbọ́ ihìn kan lati ọdọ Oluwa wá, a si ti rán ikọ̀ kan si ãrin awọn keferi, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a dide ogun si i.

OLUWA Yóo Jẹ Edomu Níyà

2 Kiyesi i, mo ti sọ iwọ di kekere larin awọn keferi: iwọ di gigàn lọpọlọpọ. 3 Irera aiya rẹ ti tàn ọ jẹ, iwọ ti ngbe inu pàlapála apáta, ibugbe ẹniti o ga: ti o nwi li ọkàn rẹ̀ pe, Tani yio mu mi sọkalẹ? 4 Bi iwọ tilẹ gbe ara rẹ ga bi idì, ati bi iwọ tilẹ tẹ́ itẹ rẹ sãrin awọn irawọ, lati ibẹ li emi o ti sọ̀ ọ kalẹ, ni Oluwa wi. 5 Bi awọn olè tọ̀ ọ wá, bi awọn ọlọṣà li oru, (bawo li a ti ke ọ kuro!) nwọn kì yio ha jale titi nwọn fi ni to? bi awọn aka-eso-ajara wá sọdọ rẹ, nwọn kì yio ha fi ẽṣẹ́ diẹ silẹ? 6 Bawo li a ti ṣawari awọn nkan Esau! bawo li a ti wá awọn ohun ikọkọ rẹ̀ jade! 7 Gbogbo awọn ẹni imulẹ rẹ ti mu ọ de opin ilẹ rẹ: awọn ti nwọn ti wà li alafia pẹlu rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si bori rẹ; awọn ti o jẹ onjẹ rẹ ti fi ọgbẹ́ si abẹ rẹ: oye kò si ninu rẹ̀. 8 Oluwa wipe, li ọjọ na ki emi o run awọn ọlọgbọn kuro ni Edomu, ati imoye kuro li oke Esau? 9 Awọn alagbara rẹ yio si bẹ̀ru, iwọ Temani, nitori ki a le ke olukuluku ti ori oke Esau kuro nitori ipania.

Àwọn Ìdí Tí A Fi Jẹ Edomu Níyà

10 Nitori ìwa-ipa si Jakobu arakunrin rẹ itiju yio bò ọ, a o si ke ọ kuro titi lai. 11 Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn. 12 Ṣugbọn iwọ kì ba ti ṣiju wo ọjọ arakunrin rẹ ni ọjọ ti on di ajeji; bẹ̃ni iwọ kì ba ti yọ̀ lori awọn ọmọ Juda ni ọjọ iparun wọn; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sọ̀rọ irera ni ọjọ wahala. 13 Iwọ kì ba ti wọ inu ibode awọn enia mi lọ li ọjọ idãmú wọn; nitotọ, iwọ kì ba ti ṣiju wo ipọnju wọn li ọjọ idãmú wọn, bẹ̃ni iwọ kì ba ti gbe ọwọ́ le ohun ini wọn li ọ̀jọ idãmú wọn. 14 Bẹ̃ni iwọ kì ba ti duro ni ikorita lati ké awọn tirẹ̀ ti o ti salà kuro; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sé awọn tirẹ̀ ti o kù li ọjọ wahala mọ.

Ọlọrun Yóo Dá Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́

15 Nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ sori gbogbo awọn keferi: bi iwọ ti ṣe, bẹ̃li a o si ṣe si ọ: ẹsan rẹ yio si yipada sori ara rẹ. 16 Nitori bi ẹnyin ti mu lori oke mimọ́ mi, bẹ̃ni gbogbo awọn keferi yio ma mu titi, nitõtọ, nwọn o mu, nwọn o si gbemì, nwọn o si wà bi ẹnipe nwọn kò ti si.

Ìṣẹ́gun Israẹli

17 Ṣugbọn igbala yio wà lori oke Sioni, yio si jẹ mimọ́, awọn ara ile Jakobu yio si ni ini wọn. 18 Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i. 19 Awọn ara gusu yio ni oke Esau; awọn ti pẹ̀tẹlẹ yio si ni awọn ara Filistia: nwọn o si ni oko Efraimu, ati oko Samaria: Benjamini yio si ni Gileadi. 20 Ati igbèkun ogun yi, ti awọn ọmọ Israeli ti o wà larin awọn ara Kenaani, titi de Sarefati; ati igbèkun Jerusalemu ti o wà ni Sefaradi, yio ni awọn ilu nla gusu. 21 Awọn olugbala yio si goke Sioni wá lati ṣe idajọ oke Esau; ijọba na yio si jẹ ti Oluwa.

Jona 1

Jona Ṣe Àìgbọràn sí OLUWA

1 NJẸ ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jona ọmọ Amittai wá, wipe, 2 Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kigbe si i; nitori ìwa buburu wọn goke wá iwaju mi. 3 Ṣugbọn Jona dide lati sá lọ si Tarṣiṣi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Joppa; o si ri ọkọ̀ kan ti nlọ si Tarṣiṣi: bẹ̃li o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ sinu rẹ̀, lati ba wọn lọ si Tarṣiṣi lati sá kuro niwaju Oluwa. 4 Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ. 5 Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra. 6 Bẹ̃li olori-ọkọ̀ tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ rò, iwọ olõrun? dide, kepe Ọlọrun rẹ, boya Ọlọrun yio ro tiwa, ki awa ki o má bà ṣegbé. 7 Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona. 8 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe? 9 On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ. 10 Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn. 11 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kini ki a ṣe si ọ, ki okun le dakẹ fun wa? nitori okun ru, o si jà ẹfufu lile. 12 On si wi fun wọn pe, Ẹ gbe mi, ki ẹ si sọ mi sinu okun; bẹ̃li okun yio si dakẹ fun nyin: nitori emi mọ̀ pe nitori mi ni ẹfufu lile yi ṣe de bá nyin. 13 Ṣugbọn awọn ọkunrin na wà kikan lati mu ọkọ̀ wá si ilẹ; ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: nitori ti okun ru, o si jà ẹfufu lile si wọn. 14 Nitorina nwọn kigbe si Oluwa nwọn si wi pe, Awa bẹ̀ ọ, Oluwa awa bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki awa ṣegbe nitori ẹmi ọkunrin yi, má si ka ẹjẹ alaiṣẹ si wa li ọrùn: nitori iwọ, Oluwa, ti ṣe bi o ti wù ọ. 15 Bẹ̃ni nwọn gbe Jona, ti nwọn si sọ ọ sinu okun: okun si dẹkun riru rẹ̀. 16 Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru Oluwa gidigidi, nwọn si rubọ si Oluwa, nwọn si jẹ́ ẹ̀jẹ́. 17 Ṣugbọn Oluwa ti pese ẹja nla kan lati gbe Jona mì. Jona si wà ninu ẹja na li ọsan mẹta ati oru mẹta.

Jona 2

Adura Jona

1 NIGBANA ni Jona gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ̀ lati inu ẹja na wá, 2 O si wipe, Emi kigbe nitori ipọnju mi si Oluwa, on si gbohùn mi; mo kigbe lati inu ipo-okú, iwọ si ti gbohùn mi. 3 Nitoriti iwọ ti sọ mi sinu ibu, larin okun; iṣàn omi si yi mi kakiri; gbogbo bibì omi ati riru omi rẹ kọja lori mi. 4 Nigbana ni mo wipe, A ta mi nù kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun ma wo iha tempili mimọ́ rẹ. 5 Omi yi mi kakiri, ani titi de ọkàn; ibu yi mi kakiri, a fi koriko-odò wé mi lori. 6 Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi. 7 Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ. 8 Awọn ti nkiyesi eke asan kọ̀ ãnu ara wọn silẹ. 9 Ṣugbọn emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjẹ́ ti mo ti jẹ. Ti Oluwa ni igbala. 10 Oluwa si sọ fun ẹja na, o si pọ̀ Jona sori ilẹ gbigbẹ.

Jona 3

Jona Gbọ́ràn sí OLUWA Lẹ́nu

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe, 2 Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ. 3 Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta. 4 Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo. 5 Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn. 6 Ọ̀rọ na si de ọdọ ọba Ninefe, o si dide kuro lori itẹ rẹ̀, o si bọ aṣọ igunwa rẹ̀ kuro lara rẹ̀, o si daṣọ ọ̀fọ bora, o si joko ninu ẽru. 7 O si kede rẹ̀, o si wi pe ki a là Ninefe ja nipa aṣẹ ọba, ati awọn agbagbà rẹ̀ pe, Máṣe jẹ ki enia, tabi ẹranko, ọwọ-ẹran tabi agbo-ẹran, tọ́ ohunkohun wò: má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi. 8 Ṣugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọ̀na ibi rẹ̀, ati kuro ni ìwa agbara ti o wà lọwọ wọn. 9 Tani le mọ̀ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rẹ̀, ki awa má ṣegbe? 10 Ọlọrun si ri iṣe wọn pe nwọn yipada kuro li ọ̀na ibi wọn: Ọlọrun si ronupiwada ibi ti on ti wi pe on o ṣe si wọn; on kò si ṣe e mọ.

Jona 4

Ibinu Jona ati Àánú Ọlọrun

1 ṢUGBỌN o bà Jona ninu jẹ́ gidigidi, o si binu pupọ̀. 2 O si gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ ọ, Oluwa, ọ̀rọ mi kọ yi nigbati mo wà ni ilẹ mi? nitorina ni mo ṣe salọ si Tarṣiṣi ni iṣaju: nitori emi mọ̀ pe, Ọlọrun olore-ọfẹ ni iwọ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi na. 3 Njẹ nitorina, Oluwa, emi bẹ ọ, gbà ẹmi mi kuro lọwọ mi nitori o sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè. 4 Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ ha ṣe rere lati binu? 5 Jona si jade kuro ni ilu na, o si joko niha ila-õrun ilu na, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ̀, o si joko ni iboji labẹ rẹ̀, titi yio fi ri ohun ti yio ṣe ilu na. 6 Oluwa Ọlọrun si pese itakùn kan, o si ṣe e ki o goke wá sori Jona; ki o le ṣiji bò o lori; lati gbà a kuro ninu ibinujẹ rẹ̀. Jona si yọ ayọ̀ nla nitori itakùn na. 7 Ṣugbọn Ọlọrun pese kokorò kan nigbati ilẹ mọ́ ni ijọ keji, o si jẹ itakùn na, o si rọ. 8 O si ṣe, nigbati õrun là, Ọlọrun si pese ẹfufu gbigbona ti ila-õrùn; õrùn si pa Jona lori, tobẹ̃ ti o rẹ̀ ẹ, o si fẹ́ ninu ara rẹ̀ lati kú, o si wipe, O sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè lọ. 9 Ọlọrun si wi fun Jona pe, O ha tọ́ fun ọ lati binu nitori itakùn na? on si wipe, O tọ́ fun mi lati binu titi de ikú. 10 Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ kẹdùn itakùn na nitori eyiti iwọ kò ṣiṣẹ, bẹ̃li iwọ kò mu u dagbà; ti o hù jade li oru kan ti o si kú li oru kan. 11 Ki emi ki o má si da Ninefe si, ilu nla nì, ninu eyiti jù ọ̀kẹ-mẹfa enia wà ti kò le mọ̀ ọtun mọ̀ osì ninu ọwọ́ wọn, ati ọ̀pọlọpọ ohun-ọsìn?

Mika 1

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Mika ara Moraṣti wá li ọjọ Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ti o ri niti Samaria ati Jerusalemu.

Ìpohùnréré Ẹkún nítorí Samaria ati Jerusalẹmu

2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá. 3 Nitori, wo o, Oluwa jade lati ipò rẹ̀ wá, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ awọn ibi giga aiye mọlẹ. 4 Awọn oke nla yio si yọ́ labẹ rẹ̀, awọn afonifojì yio si pinyà, bi ida niwaju iná, bi omi ti igbálọ ni ibi gẹ̀rẹgẹ̀rẹ. 5 Nitori irekọja Jakobu ni gbogbo eyi, ati nitori ẹ̀ṣẹ ile Israeli. Kini irekọja Jakobu? Samaria ha kọ? ki si ni awọn ibi giga Juda? Jerusalemu ha kọ? 6 Nitorina li emi o ṣe Samaria bi òkiti pápa, ati bi gbigbin àjara: emi o si gbá awọn okuta rẹ̀ danù sinu afonifojì, emi o si ṣi awọn ipalẹ rẹ̀ silẹ. 7 Gbogbo awọn ere fifin rẹ̀ ni a o run womu-womu, gbogbo awọn ẹbùn rẹ̀ li a o fi iná sun, gbogbo awọn oriṣà rẹ̀ li emi o sọ di ahoro: nitoriti o ko o jọ lati inu ẹbùn panṣaga wá, nwọn o si pada si ẹbùn panṣaga. 8 Nitori eyi li emi o ṣe pohunrere, ti emi o si ma hu, emi o ma lọ ni ẹsẹ lasan, ati ni ihòho: emi o pohunrere bi dragoni, emi o si ma kedaro bi awọn ọmọ ògongo. 9 Nitori ti ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ alailewòtan; nitoriti o wá si Juda; on de ẹnu-bode awọn enia mi, ani si Jerusalemu.

Ọ̀tá Súnmọ́ Jerusalẹmu

10 Ẹ máṣe sọ ni Gati, ẹ máṣe sọkun rara: ni ile Afra mo yi ara mi ninu ekuru. 11 Ẹ kọja lọ, iwọ ará Safiri, pẹlu itiju rẹ ni ihòhò: ara Saanani kò jade wá; ọ̀fọ̀ Beteseli yio gba iduro rẹ̀ lọwọ nyin. 12 Nitori ara Maroti nreti ire, ṣugbọn ibi sọkalẹ ti ọdọ Oluwa wá si ẹnu bode Jerusalemu. 13 Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ. 14 Nitorina ni iwọ o ṣe fi iwe ikọ̀silẹ fun Moreṣetigati: awọn ile Aksibi yio jẹ eke si awọn ọba Israeli. 15 Sibẹ̀ emi o mu arole kan fun ọ wá, Iwọ ara Mareṣa: ogo Israeli yio wá si Adullamu. 16 Sọ ara rẹ di apari, si rẹ́ irun rẹ nitori awọn ọmọ rẹ ẹlẹgẹ́; sọ apári rẹ di gbòro bi idì; nitori a dì wọn ni igbèkun lọ kuro lọdọ rẹ.

Mika 2

Ìjìyà fún Àwọn Tí Wọn ń Ni Àwọn Talaka Lára

1 EGBE ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede, ti nṣiṣẹ ibi lori akete wọn! nigbati ojumọ́ mọ́ nwọn nṣe e, nitoripe o wà ni agbara ọwọ́ wọn. 2 Nwọn si nṣe ojukòkoro oko, nwọn si nfi ipá gbà a: ati ile, nwọn a si mu wọn lọ: nwọn si ni enia lara ati ile rẹ̀, ani enia ati ini rẹ̀. 3 Nitorina bayi ni Oluwa wi; Kiyesi i, emi ngbimọ̀ ibi si idile yi, ninu eyiti ọrùn nyin kì yio le yọ; bẹni ẹnyin kì yio fi igberaga lọ: nitori akokò ibi ni yi. 4 Li ọjọ na ni ẹnikan yio pa owe kan si nyin, yio si pohunrere-ẹkun kikorò pe, Ni kikó a kó wa tan? on ti pin iní enia mi: bawo ni o ti ṣe mu u kuro lọdọ mi! o ti pin oko wa fun awọn ti o yapa. 5 Nitorina iwọ kì yio ni ẹnikan ti yio ta okùn nipa ìbo ninu ijọ enia Oluwa. 6 Nwọn ni, ẹ máṣe sọtẹlẹ, nwọn o sọtẹlẹ, bi nwọn kò ba sọtẹlẹ bayi, itiju kì yio kuro. 7 Iwọ ẹniti anpe ni ile Jakobu, Ẹmi Oluwa ha bùkù bi? iṣe rẹ̀ ha ni wọnyi? ọ̀rọ mi kò ha nṣe rere fun ẹni ti nrin dẽde bi? 8 Ati nijelo awọn enia mi dide bi ọta si mi: ẹnyin ti bọ́ ẹ̀wu ati aṣọ ibora kuro lọdọ awọn ti nkọja li ailewu, bi awọn ẹniti o kọ̀ ogun silẹ. 9 Obinrin awọn enia mi li ẹnyin ti le jade kuro ninu ile wọn daradara; ẹnyin ti gbà ogo mi kuro lọwọ awọn ọmọ wọn lailai. 10 Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi kì iṣe ibi isimi: nitoriti o jẹ alaimọ́, yio pa nyin run, ani iparun kikorò? 11 Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi. 12 Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia. 13 Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.

Mika 3

Mika Bá Àwọn Olórí Israẹli Wí

1 EMI si wipe, Gbọ́, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ni Jakobu, ati ẹnyin alakoso ile Israeli; ti nyin kì iṣe lati mọ̀ idajọ bi? 2 Ẹnyin ti o korira ire, ti ẹ si fẹ ibi; ti ẹ já awọ-ara wọn kuro lara wọn, ati ẹran-ara wọn kuro li egungun wọn; 3 Awọn ẹniti o si jẹ ẹran-ara awọn enia mi pẹlu, ti nwọn si họ́ awọ-ara wọn kuro lara wọn, nwọn si fọ́ egungun wọn, nwọn si ke wọn wẹwẹ, bi ti ikòko, ati gẹgẹ bi ẹran ninu òdu. 4 Nigbana ni nwọn o kigbe pe Oluwa, ṣugbọn on kì yio gbọ́ ti wọn: on o tilẹ pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ wọn li akoko na, gẹgẹ bi nwọn ti huwà alaifi ri ninu gbogbo iṣe wọn. 5 Bayi ni Oluwa wi niti awọn woli ti nṣì awọn enia mi li ọ̀na, ti nfi ehín wọn bù ni ṣán, ti o si nkigbe wipe, Alafia; on ẹniti kò fi nkan si wọn li ẹnu, awọn na si mura ogun si i. 6 Nitorina oru yio ru nyin, ti ẹnyin kì yio fi ri iran; òkunkun yio si kùn fun nyin, ti ẹnyin kì o fi le sọtẹlẹ; õrùn yio si wọ̀ lori awọn woli, ọjọ yio si ṣokùnkun lori wọn. 7 Oju yio si tì awọn ariran, awọn alasọtẹlẹ̀ na yio si dãmu: nitõtọ, gbogbo wọn o bò ete wọn: nitori idahùn kò si lati ọdọ Ọlọrun. 8 Ṣugbọn nitõtọ emi kún fun agbara nipa ẹmi Oluwa, ati fun idajọ, ati fun ipá, lati sọ irekọja Jakobu fun u, ati lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli fun u. 9 Gbọ́ eyi, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ile Jakobu; ati awọn alakoso ile Israeli, ti o korira idajọ, ti o si yi otitọ pada. 10 Ti o fi ẹjẹ kọ́ Sioni, ati Jerusalemu pẹlu iwà ẹ̀ṣẹ. 11 Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa. 12 Nitorina nitori nyin ni a o ṣe ro Sioni bi oko, Jerusalemu yio si di okìti, ati oke-nla ile bi ibi giga igbo.

Mika 4

Ìjọba Alaafia OLUWA Tí Ó Kárí Ayé

1 YIO si ṣe li ọjọ ikẹhìn, a o fi oke ile Oluwa kalẹ lori awọn oke-nla, a o si gbe e ga jù awọn oke kekeke lọ; awọn enia yio si mã wọ́ sinu rẹ̀. 2 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. 3 On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. 4 Ṣugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan kì yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu Oluwa awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ. 5 Nitori gbogbo awọn enia ni yio ma rìn, olukuluku li orukọ ọlọrun tirẹ̀, awa o si ma rìn li orukọ Oluwa Ọlọrun wa lai ati lailai.

Israẹli Yóo Pada láti Oko Ẹrú

6 Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó amukun, emi o si ṣà ẹniti a le jade, ati ẹniti emi ti pọn loju jọ; 7 Emi o si dá awọn amukun si fun iyokù, emi o si sọ ẹniti a ta nù rére di orilẹ-ède alagbara: Oluwa yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni lati isisiyi lọ, ati si i lailai. 8 Ati iwọ, Ile iṣọ agbo agùtan, odi ọmọbinrin Sioni, si ọdọ rẹ ni yio wá, ani ijọba iṣãju; ijọba yio si wá si ọdọ ọmọbinrin Jerusalemu. 9 Njẹ kini iwọ ha nkigbe soke si? ọba kò ha si ninu rẹ? awọn ìgbimọ rẹ ṣegbé bi? nitori irora ti dì ọ mu bi obinrin ti nrọbi. 10 Ma rọbi, si bi, ọmọbinrin Sioni, bi ẹniti nrọbi: nitori nisisiyi ni iwọ o jade lọ kuro ninu ilu, iwọ o si ma gbe inu igbẹ́, iwọ o si lọ si Babiloni; nibẹ̀ ni a o gbà ọ; nibẹ̀ ni Oluwa yio rà ọ padà kuro lọwọ awọn ọta rẹ. 11 Ati nisisiyi ọ̀pọlọpọ orile-ède gbá jọ si ọ, ti nwi pe, jẹ ki a sọ ọ di aimọ́, si jẹ ki oju wa ki o wo Sioni. 12 Ṣugbọn nwọn kò mọ̀ erò Oluwa, bẹ̃ni oye ìmọ rẹ̀ kò ye wọn: nitori on o kó wọn jọ bi ití sinu ipaka. 13 Dide, si ma pakà, Iwọ ọmọbinrin Sioni: nitori emi o sọ iwo rẹ di irin, emi o si sọ patakò rẹ di idẹ, iwọ o si run ọ̀pọlọpọ enia womu-womu: emi o si yá ère wọn sọtọ̀ fun Oluwa, ati iní wọn si Oluwa gbogbo aiye.

Mika 5

1 NISISIYI gbá ara rẹ jọ li ọwọ́, Iwọ ọmọbinrin ọwọ́: o ti dó tì wa; nwọn o fi ọ̀pa lu onidajọ Israeli li ẹ̀rẹkẹ.

Ọlọrun Ṣèlérí láti Yan Olórí ní Bẹtlẹhẹmu

2 Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye. 3 Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli. 4 On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye. 5 Eleyi ni yio jẹ alafia, nigbati ara Assiria yio wá si ilẹ wa; nigbati yio si tẹ̀ awọn ãfin wa mọlẹ, nigba nã li awa o gbe oluṣọ agutan meje dide si i, ati olori enia mẹjọ.

Ìdásílẹ̀ ati Ìjìyà

6 Nwọn o si fi idà pa ilẹ Assiria run, ati ilẹ Nimrodu ni àbawọ̀ inu rẹ̀: yio si gbà wa lọwọ ara Assiria nigbati o ba wá ilẹ wa, ati nigbati o ba si ntẹ̀ àgbegbe wa mọlẹ. 7 Iyokù Jakobu yio si wà lãrin ọ̀pọ enia bi irì lati ọdọ Oluwa wá, bi ọwarà òjo lori koriko, ti kì idara duro de enia, ti kì isi duro de awọn ọmọ enia. 8 Iyokù Jakobu yio si wà lãrin awọn Keferi, lãrin ọ̀pọ enia bi kiniun, lãrin awọn ẹranko igbo, bi ọmọkiniun lãrin agbo agutan; eyiti, bi o ba là a ja, ti itẹ̀ mọlẹ, ti isi ifa ya pẹrẹpẹrẹ, kò si ẹniti yio gbalà. 9 A o gbe ọwọ́ rẹ soke sori awọn ọ̀ta rẹ, gbogbo awọn ọ̀ta rẹ, li a o si ke kuro. 10 Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa wi, ti emi o ke awọn ẹṣin rẹ kuro lãrin rẹ, emi o si pa awọn kẹkẹ́ ogun rẹ run. 11 Emi o si ke ilu-nla ilẹ rẹ kuro, emi o si tì gbogbo odi rẹ ṣubu: 12 Emi o si ke iwà-ajẹ kuro lọwọ rẹ: iwọ kì yio si ni alafọ̀ṣẹ mọ: 13 Ere fifin rẹ pẹlu li emi o ke kuro, awọn ere rẹ kuro lãrin rẹ; iwọ kì o si ma sin iṣẹ ọwọ́ rẹ mọ. 14 Emi o si tú igbo òriṣa rẹ kuro lãrin rẹ: emi o si pa awọn ilu rẹ run. 15 Emi o si gbẹsan ni ibinu ati irunu lara awọn keferi, ti nwọn kò ti igbọ́ ri.

Mika 6

Ọlọrun bá Israẹli Rojọ́

1 Ẹ gbọ́ nisisiyi ohun ti Oluwa wi; Dide, ba oke nla wijọ, si jẹ ki oke kékèké gbohùn rẹ. 2 Ẹ gbọ́ ẹjọ Oluwa, ẹnyin oke-nla, ati ẹnyin ipilẹ ilẹ̀ aiye: nitori Oluwa mba awọn enia rẹ̀ wijọ, yio si ba Israeli rojọ. 3 Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara? dahùn si i. 4 Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ. 5 Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.

Ohun Tí OLUWA Fẹ́ Kí Á Ṣe

6 Kini emi o ha mu wá siwaju Oluwa, ti emi o fi tẹ̀ ara mi ba niwaju Ọlọrun giga? ki emi ha wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun, pẹlu ọmọ malu ọlọdún kan? 7 Inu Oluwa yio ha dùn si ẹgbẹgbẹ̀run àgbo, tabi si ẹgbẹgbãrun iṣàn òroro? emi o ha fi àkọbi mi fun irekọja mi, iru-ọmọ inu mi fun ẹ̀ṣẹ ọkàn mi? 8 A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ? 9 Ohùn Oluwa kigbe si ilu na, ọlọgbọ́n yio si ri orukọ rẹ; ẹ gbọ́ ọ̀pa na, ati ẹniti o yàn a? 10 Iṣura ìwa buburu ha wà ni ile enia buburu sibẹ̀, ati òṣuwọ̀n aikún ti o jẹ ohun ibinú? 11 Ki emi ha kà wọn si mimọ́ pẹlu òṣuwọ̀n buburu, ati pẹlu àpo òṣuwọ̀n ẹ̀tan? 12 Ti awọn ọlọrọ̀ rẹ̀ kún fun ìwa-ipá, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ ti sọ̀rọ eké, ahọn wọn si kún fun ẹ̀tan li ẹnu wọn. 13 Nitorina pẹlu li emi o ṣe mu ọ ṣàisan ni lilù ọ, ni sisọ ọ dahoro nitori ẹ̀ṣẹ rẹ. 14 Iwọ o jẹun, ṣugbọn iwọ kì yio yo; idábẹ yio wà lãrin rẹ; iwọ o kó kuro, ṣugbọn iwọ kì o lọ lailewu; ati eyi ti o kó lọ li emi o fi fun idà. 15 Iwọ o gbìn, ṣugbọn iwọ kì yio ká; iwọ o tẹ̀ igi olifi, ṣugbọn iwọ kì o fi ororo kunra; ati eso àjara, sugbọn iwọ kì o mu ọti-waini. 16 Nitori ti a pa aṣẹ Omri mọ́, ati gbogbo iṣẹ ile Ahabu, ẹ si rìn ni ìmọ wọn; ki emi ba le sọ ọ di ahoro, ati awọn ti ngbe inu rẹ di ẹ̀gan: ẹnyin o si rù ẹgan enia mi.

Mika 7

Ìwà Ìbàjẹ́ Israẹli

1 EGBE ni fun mi! nitori emi dàbi ikojọpọ̀ eso ẹ̃rùn, bi ẽṣẹ́ ikorè eso àjara: kò si ití kan lati jẹ: akọso ti ọkàn mi fẹ. 2 Oninurere ti run kuro li aiye: kò si si olotitọ kan ninu enia: gbogbo wọn ba fun ẹ̀jẹ, olukuluku wọn nfi àwọn dẹ arakunrin rẹ̀. 3 Ọwọ́ wọn ti mura tan lati ṣe buburu, olori mbère, onidajọ si mbère fun ẹsan; ẹni-nla nsọ ìro ika rẹ̀, nwọn si nyi i po. 4 Ẹniti o sànjulọ ninu wọn dàbi ẹ̀gun: ìduroṣiṣin julọ mú jù ẹgún ọgbà lọ: ọjọ awọn olùṣọ rẹ ati ti ìbẹwo rẹ de; nisisiyi ni idãmu wọn o de. 5 Ẹ má gba ọrẹ́ kan gbọ́, ẹ má si gbẹkẹ̀le amọ̀na kan: pa ilẹkùn ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sùn ni õkan-àiya rẹ. 6 Nitori ọmọkunrin nṣàibọ̀wọ fun baba, ọmọbinrin dide si ìya rẹ̀, aya-ọmọ si iyakọ rẹ̀; ọta olukuluku ni awọn ara ile rẹ̀. 7 Nitorina emi o ni ireti si Oluwa: emi o duro de Ọlọrun igbala mi: Ọlọrun mi yio gbọ́ temi.

OLUWA Mú Ìgbàlà Wá

8 Má yọ̀ mi, Iwọ ọta mi: nigbati mo ba ṣubu, emi o dide; nigbati mo ba joko li okùnkun, Oluwa yio jẹ imọlẹ fun mi. 9 Emi o rù ibinu Oluwa, nitori emi ti dẹṣẹ si i, titi yio fi gbà ẹjọ mi rò, ti yio si ṣe idajọ mi; yio mu mi wá si imọlẹ, emi o si ri ododo rẹ̀. 10 Nitori ọta mi yio ri i, itiju yio si bò ẹniti o wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun rẹ wà? oju mi yio ri i, nisisiyi ni yio di itẹ̀mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita. 11 Ọjọ ti a o mọ odi rẹ, ọjọ na ni aṣẹ yio jinà rére. 12 Ọjọ na ni nwọn o si ti Assiria wá sọdọ rẹ, ati lati ilu olodi, ati lati ile iṣọ́ alagbara titi de odò, ati lati okun de okun, ati oke-nla de oke-nla. 13 Ilẹ na yio si di ahoro fun awọn ti ngbe inu rẹ̀, nitori eso ìwa wọn.

Àánú OLUWA Lórí Israẹli

14 Fi ọpa rẹ bọ́ enia agbo ini rẹ, ti ndágbe inu igbó lãrin Karmeli: jẹ ki wọn jẹ̀ ni Baṣani ati Gileadi, bi ọjọ igbãni. 15 Bi ọjọ ti o jade kuro ni ilẹ Egipti li emi o fi ohun iyanu han a. 16 Awọn orilẹ-ède yio ri, oju o si tì wọn ninu gbogbo agbara wọn: nwọn o fi ọwọ́ le ẹnu, eti wọn o si di. 17 Nwọn o lá erùpẹ bi ejò, nwọn o si jade kuro ninu ihò wọn bi ekòlo ilẹ: nwọn o bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa, nwọn o si bẹ̀ru nitori rẹ. 18 Tani Ọlọrun bi iwọ, ti o ndari aiṣedede jì, ti o nre iyokù ini rẹ̀ kọja? kò dá ibinu rẹ̀ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ãnu. 19 Yio yipadà, yio ni iyọnú si wa; yio si tẹ̀ aiṣedede wa ba; iwọ o si sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn sinu ọgbun okun. 20 Iwọ o fi otitọ fun Jakobu, ãnu fun Abrahamu, ti iwọ ti bura fun awọn baba wa, lati ọjọ igbani.

Nahumu 1

1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi.

Ibinu OLUWA sí Ìlú Ninefe

2 Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀. 3 Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀. 4 O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ. 5 Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. 6 Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata. 7 Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e. 8 Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀. 9 Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji. 10 Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin. 11 Ẹnikan ti ọdọ rẹ jade wá, ti o ngbirò ibi si Oluwa, olugbìmọ buburu. 12 Bayi ni Oluwa wi; bi nwọn tilẹ pé, ti nwọn si pọ̀ niye, ṣugbọn bayi ni a o ke nwọn lulẹ, nigbati on o ba kọja. Bi mo tilẹ ti pọn ọ loju, emi kì yio pọn ọ loju mọ. 13 Nitori nisisiyi li emi o fà ajàga rẹ̀ kuro li ọrun rẹ, emi o si dá idè rẹ wọnni li agbede-meji. 14 Oluwa si ti fi aṣẹ kan lelẹ nitori rẹ pe, ki a má ṣe gbìn ninu orukọ rẹ mọ: lati inu ile ọlọrun rẹ wá li emi o ke ere fifin ati ere didà kuro: emi o wà ibojì rẹ; nitori ẹgbin ni iwọ. 15 Wò o lori oke nla ẹsẹ̀ ẹniti o mu ihìn rere wá, ẹniti o nkede alafia! Iwọ Juda, pa aṣẹ rẹ ti o ni irònu mọ, san ẹ̀jẹ́ rẹ: nitori enia buburu kì yio kọja lãrin rẹ mọ; a ti ké e kuro patapata.

Nahumu 2

Ìṣubú Ninefe

1 ATUNIKA de iwaju rẹ (Ninefe): pa ile-iṣọ mọ, ṣọ ọ̀na na, di àmurè ẹ̀gbẹ rẹ ko le, mura girigiri. 2 Nitori Oluwa tun pada si ọlanla Jakobu, gẹgẹ bi ọlanla Israeli: atunidanù ti tú wọn danù, nwọn si ba ẹka àjara wọn jẹ. 3 A sọ asà awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ di pupa, awọn akin wọn wọ̀ odòdó: kẹkẹ́ ogun yio ma kọ bi iná li ọjọ ipèse rẹ̀, igi firi li a o si mì tìti. 4 Ariwo kẹkẹ́ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọ̀na gbigbòro, nwọn o dabi etùfu, nwọn o kọ́ bi mànamána. 5 On o ṣe aṣàro awọn ọlọla rẹ̀: nwọn o kọsẹ̀ ni irìn wọn; nwọn o yara si ibi odi rẹ̀, a o si pèse ãbo rẹ̀. 6 A o ṣi ilẹ̀kun odò wọnni silẹ, a o si sọ ãfin na di yiyọ́. 7 Eyi ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ li a o si dì ni igbèkun lọ, a o si mu u goke wá, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ yio fi ohùn bi ti oriri ṣe amọ̀na rẹ̀, nwọn a ma lù aiya wọn. 8 Ṣugbọn Ninefe li ọjọ ti o ti wà bi adagun omi: sibẹ̀ nwọn o salọ kuro. Duro, duro! ni nwọn o ma ke; ṣugbọn ẹnikan kì yio wò ẹhìn. 9 Ẹ ko ikogun fàdakà, ẹ ko ikogun wurà! ati iṣura wọn ailopin na, ati ogo kuro ninu gbogbo ohunelò ti a fẹ́. 10 On ti sòfo, o ti di asan, o si di ahoro: aiyà si yọ́, ẽkún nlù ara wọn, irora pupọ̀ si wà ninu gbogbo ẹgbẹ́, ati oju gbogbo wọn si kó dudu jọ. 11 Nibo ni ibugbé awọn kiniun wà, ati ibujẹ awọn ọmọ kiniun, nibiti kiniun, ani agbà kiniun, ti nrìn, ati ọmọ kiniun, kò si si ẹniti o dẹruba wọn? 12 Kiniun ti fàya pẹrẹpẹrẹ tẹrùn fun awọn ọmọ rẹ̀, o si fun li ọrun pa fun awọn abo kiniun rẹ̀, o si fi ohun ọdẹ kún isà rẹ̀, ati ihò rẹ̀ fun onjẹ agbara. 13 Kiyesi i, emi dojukọ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, emi o si fi kẹkẹ́ rẹ̀ wọnni joná ninu ẹ̃fin, idà yio si jẹ ọmọ kiniun rẹ wọnni run: emi o si ke ohun ọdẹ rẹ kuro lori ilẹ aiye, ohùn awọn ojiṣẹ rẹ li a kì yio si tún gbọ́ mọ.

Nahumu 3

1 EGBE ni fun ilu ẹjẹ̀ nì! gbogbo rẹ̀ kun fun eké, ati olè, ijẹ kò kuro; 2 Ariwo pàṣan, ati ariwo kikùn kẹkẹ́, ati ti ijọ awọn ẹṣin, ati ti fifò kẹkẹ́. 3 Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni: 4 Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀. 5 Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba. 6 Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà. 7 Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ? 8 Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá? 9 Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ. 10 Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì. 11 Iwọ pẹlu o si yó ọti; a o si fi ọ pamọ, iwọ pẹlu o si ma ṣe afẹri ãbò nitori ti ọta na. 12 Gbogbo ile-iṣọ agbara rẹ yio dabi igi ọpọ̀tọ pẹlu akọpọn ọpọ̀tọ: bi a ba gbọ̀n wọn, nwọn o si bọ si ẹnu ọjẹun. 13 Kiye si i, obinrin li awọn enia rẹ lãrin rẹ: oju ibodè ilẹ rẹ li a o ṣi silẹ gbaguda fun awọn ọta rẹ: iná yio jo ikere rẹ. 14 Iwọ pọn omi de ihamọ, mu ile iṣọ rẹ le: wọ̀ inu amọ̀, ki o si tẹ̀ erupẹ̀, ki o si ṣe ibiti a nsun okuta-amọ̀ ki o le. 15 Nibẹ̀ ni iná yio jo ọ run; idà yio ké ọ kuro, yio si jẹ ọ bi kòkoro: sọ ara rẹ di pupọ̀ bi kòkoro, si sọ ara rẹ di pupọ̀ bi ẽṣu. 16 Iwọ ti sọ awọn oniṣòwo rẹ di pupọ̀ jù iràwọ oju ọrun lọ: kokòro nà ara rẹ̀, o si fò lọ. 17 Awọn alade rẹ dabi eṣú, awọn ọgagun rẹ si dabi ẹlẹngà nla, eyiti ndó sinu ọgbà la ọjọ otutù, ṣugbọn nigbati õrùn là, nwọn sa lọ, a kò si mọ̀ ibiti wọn gbe wà. 18 Awọn olùṣọ agùtan rẹ ntõgbe, Iwọ ọba Assiria: awọn ọlọla rẹ yio ma gbe inu ekuru: awọn enia rẹ si tuka lori oke-nla, ẹnikan kò si kó wọn jọ. 19 Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?

Habakuku 1

1 Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí.

Ìṣubú Ninefe

2 Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà! 3 Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ. 4 Nitorina li ofin ṣe di ẹ̀rọ, ti idajọ kò si jade lọ li ẹtọ́; nitoriti ẹni buburu yí olododo ka; nitorina ni idajọ ẹbi ṣe njade.

Ìdáhùn Ọlọrun

5 Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin. 6 Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn. 7 Nwọn ni ẹ̀ru, nwọn si fò ni laiyà: idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yio ma ti inu wọn jade. 8 Ẹṣin wọn pẹlu yara jù ẹkùn lọ, nwọn si muná jù ikõkò aṣãlẹ lọ: ẹlẹṣin wọn yio si tàn ara wọn ka, ẹlẹṣin wọn yio si ti ọ̀na jijìn rére wá; nwọn o si fò bi idì ti nyára lati jẹun. 9 Gbogbo wọn o si wá fun ìwa-ipá; iwò oju wọn o si wà siwaju, nwọn o si kó igbèkun jọ bi yanrìn. 10 Nwọn o si ma fi awọn ọba ṣẹsín, awọn ọmọ alade yio si di ẹni-ẹ̀gan fun wọn: gbogbo ibi agbara ni nwọn o si fi rẹrin; nitoripe nwọn o ko erupẹ̀ jọ, nwọn o si gbà a. 11 Nigbana ni inu rẹ̀ yio yipadà, yio si rekọja, yio si ṣẹ̀, ni kikà agbara rẹ̀ yi si iṣẹ òriṣa rẹ̀.

Habakuku tún Ráhùn sí OLUWA

12 Lati aiyeraiye ki iwọ ti wà? Oluwa Ọlọrun mi, Ẹni Mimọ́ mi? awa kì yio kú. Oluwa, iwọ ti yàn wọn fun idajọ; Ọlọrun alagbara, iwọ ti fi ẹsẹ̀ wọn mulẹ fun ibawi. 13 Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run? 14 Ti iwọ si nṣe enia bi ẹja okun, bi ohun ti nrakò, ti kò ni alakoso lori wọn? 15 Iwọ ni àwọn lati fi gbé gbogbo wọn, nwọn nfi àwọn mu wọn, nwọn si nfi awò wọn kó wọn: nitorina ni nwọn ṣe nyọ̀, ti inu wọn si ndùn. 16 Nitorina, nwọn nrubọ si àwọn wọn, nwọn si nsùn turari fun awò wọn; nitori nipa wọn ni ipin wọn ṣe li ọrá, ti onjẹ wọn si fi di pupọ̀. 17 Nitorina, nwọn o ha ma dà àwọn wọn, nwọn kì yio ha dẹkun lati ma fọ́ orilẹ-ède gbogbo?

Habakuku 2

Ìdáhùn OLUWA sí Habakuku

1 LORI ibuṣọ́ mi li emi o duro, emi o si gbe ara mi kà ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yio sọ fun mi, ati èsi ti emi o fọ́, nigbati a ba mba mi wi. 2 Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare. 3 Nitori iran na jẹ ti igbà kan ti a yàn, yio ma yára si igbẹhìn, kì yio si ṣeke, bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè e, nitori ni dide, yio de, kì yio pẹ. 4 Kiyesi i, ọkàn rẹ̀ ti o gbega, kò duro ṣinṣin ninu rẹ̀: ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀.

Ìjìyà Àwọn Alaiṣododo

5 Bẹ̃ni pẹlu, nitoriti ọti-waini li ẹtàn, agberaga enia li on, kì isi simi, ẹniti o sọ ifẹ rẹ̀ di gbigbõrò bi ipò-okú, o si dabi ikú, a kò si lè tẹ́ ẹ lọrun, ṣugbọn o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si ọdọ, o si gbá gbogbo enia jọ si ọdọ rẹ̀: 6 Gbogbo awọn wọnyi kì yio ma pa owe si i, ti nwọn o si ma kọ orin owe si i, wipe, Egbe ni fun ẹniti nmu ohun ti kì iṣe tirẹ̀ pọ̀ si i! yio ti pẹ to? ati fun ẹniti ndi ẹrẹ̀ ilọnilọwọgbà ru ara rẹ̀. 7 Awọn ti o yọ ọ lẹnu, kì yio ha dide lojiji? awọn ti o wahalà rẹ kì yio ha ji? iwọ kì yio ha si di ikogun fun wọn? 8 Nitori iwọ ti kó orilẹ-ède pupọ̀, gbogbo iyokù awọn enia na ni yio kó ọ; nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa-ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. 9 Egbe ni fun ẹniti njẹ erè ijẹkujẹ si ile rẹ̀, ki o lè ba gbe itẹ́ rẹ̀ ka ibi giga, ki a lè ba gbà a silẹ kuro lọwọ ibi! 10 Iwọ ti gbìmọ itìju si ile rẹ, nipa kike enia pupọ̀ kuro, o si ti ṣẹ̀ si ọkàn rẹ. 11 Nitoriti okuta yio kigbe lati inu ogiri wá, ati igi-idábu lati inu òpo wá yio si da a lohùn. 12 Egbe ni fun ẹniti o fi ẹjẹ̀ kọ ilu, ti o si fi aiṣedede tẹ̀ ilu nla do. 13 Kiyesi i, ti Oluwa awọn ọmọ-ogun kọ́ pe, ki awọn enia na ma ṣe lãla fun iná, ati ki awọn enia na si ma ṣe ara wọn li ãrẹ̀ fun asan? 14 Nitoriti aiye yio kún fun ìmọ ogo Oluwa, bi omi ti bò okun. 15 Egbe ni fun ẹniti o fi ohun mimu fun aladugbo rẹ̀, ti o si fi ọti-lile rẹ fun u, ti o si jẹ ki o mu amupara pẹlu, ki iwọ ba le wò ihòho wọn! 16 Itìju bò ọ nipò ogo, iwọ mu pẹlu, ki abẹ́ rẹ le hàn, ago ọwọ́ ọtun Oluwa ni a o yipadà si ọ, ati itọ́ itìju sára ogo rẹ. 17 Nitori ti ìwa-ipá ti Lebanoni yio bò ọ, ati ikogun awọn ẹranko, ti o bà wọn li ẹ̀ru, nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. 18 Erè kini ere fínfin nì, ti oniṣọna rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ; ere didà, ati olùkọ eké, ti ẹniti nṣe iṣẹ rẹ̀ fi gbẹkẹ̀le e, lati ma ṣe ere ti o yadi? 19 Egbe ni fun ẹniti o wi fun igi pe, Ji; fun okuta ti o yadi pe, Dide, on o kọ́ ni! Kiyesi i, wurà ati fàdakà li a fi bò o yika, kò si si ẽmi kan ninu rẹ̀. 20 Ṣugbọn Oluwa mbẹ ninu tempili rẹ̀ mimọ́; jẹ ki gbogbo aiye pa rọ́rọ niwaju rẹ̀.

Habakuku 3

Adura Habakuku

1 ADURA Habakuku woli lara Sigionoti. 2 Oluwa, mo ti gbọ́ ohùn rẹ, ẹ̀ru si bà mi: Oluwa, mu iṣẹ rẹ sọji lãrin ọdun, lãrin ọdun sọ wọn di mimọ̀; ni ibinu ranti ãnu. 3 Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀. 4 Didán rẹ̀ si dabi imọlẹ; itanṣan nti iha rẹ̀ wá: nibẹ̀ si ni ipamọ agbara rẹ̀ wà. 5 Ajàkalẹ arùn nlọ niwaju rẹ̀, ati okunrun njade lati ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ. 6 O duro, o si wọ̀n ilẹ aiye: o wò, o si mu awọn orilẹ-ède warìri; a si tú awọn oke-nla aiyeraiye ká, awọn òkèkékèké aiyeraiye si tẹba: ọ̀na rẹ̀ aiyeraiye ni. 7 Mo ri agọ Kuṣani labẹ ipọnju: awọn aṣọ-ikele ilẹ̀ Midiani si warìri. 8 Oluwa ha binu si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si okun, ti iwọ fi ngùn ẹṣin rẹ ati kẹkẹ́ igbàla rẹ? 9 A ṣi ọrun rẹ̀ silẹ patapata, gẹgẹ bi ibura awọn ẹ̀ya, ani ọ̀rọ rẹ. Iwọ ti fi odò là ilẹ aiye. 10 Awọn oke-nla ri ọ, nwọn si warìri: akúnya omi kọja lọ: ibú fọ̀ ohùn rẹ̀, o si gbe ọwọ́ rẹ̀ si oke. 11 Õrùn ati oṣupa duro jẹ ni ibùgbe wọn: ni imọlẹ ọfà rẹ ni nwọn lọ, ati ni didán ọ̀kọ rẹ ti nkọ màna. 12 Ni irúnu ni iwọ rìn ilẹ na ja, ni ibinu ni iwọ ti tẹ̀ awọn orilẹ-ede rẹ́. 13 Iwọ jade lọ fun igbàla awọn enia rẹ, fun igbàla ẹni atororosi rẹ; iwọ ti ṣá awọn olori kuro ninu ile awọn enia buburu, ni fifi ipinlẹ hàn titi de ọrùn. 14 Iwọ ti fi ọ̀pa rẹ̀ lu awọn olori iletò rẹ̀ já: nwọn rọ́ jade bi ãjà lati tu mi ka: ayọ̀ wọn ni bi ati jẹ talakà run nikọ̀kọ. 15 Iwọ fi awọn ẹṣin rẹ rìn okun ja, okìti omi nla. 16 Nigbati mo gbọ́, ikùn mi warìri; etè mi gbọ̀n li ohùn na; ibàjẹ wọ̀ inu egungun mi lọ, mo si warìri ni inu mi, ki emi ba le simi li ọjọ ipọnju: nigbati o ba goke tọ̀ awọn enia lọ, yio ke wọn kuro. 17 Bi igi ọpọ̀tọ kì yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko kì yio si mu onje wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ́ ẹran kì yio si si ni ibùso mọ: 18 Ṣugbọn emi o ma yọ̀ ninu Oluwa, emi o ma yọ̀ ninu Ọlọrun igbàla mi. 19 Oluwa Ọlọrun ni agbara mi, on o si ṣe ẹsẹ̀ mi bi ẹsẹ̀ agbọ̀nrin, lori ibi giga mi ni yio si mu mi rìn. Si olori akọrin lara ohun-ọnà orin olokùn mi.

Sefaniah 1

1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Sefaniah wá ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hisikiah, li ọjọ Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda.

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọrun

2 Oluwa wipe, emi o mu gbogbo nkan kuro lori ilẹ na patapata. 3 Emi o mu enia ati ẹranko kuro; emi o mu ẹiyẹ oju ọrun kuro, ati ẹja inu okun, ati ohun idigbòlu pẹlu awọn enia buburu; emi o si ké enia kuro lori ilẹ, ni Oluwa wi. 4 Emi o nà ọwọ́ mi pẹlu sori Juda, ati sori gbogbo ara Jerusalemu; emi o si ké iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa; 5 Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori orule: awọn ti nsìn, ti nfi Oluwa bura, ti si nfi Malkomu bura; 6 Ati awọn ẹniti o yipadà kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ẹniti kò ti wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère rẹ̀. 7 Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ: nitori Oluwa ti pesè ẹbọ kan silẹ̀, o si ti yà awọn alapèjẹ rẹ̀ si mimọ́. 8 Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ Oluwa, ti emi o bẹ̀ awọn olori wò, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo iru awọn ti o wọ̀ ajèji aṣọ. 9 Li ọjọ na gan li emi o bẹ̀ gbogbo awọn ti nfò le iloro wò pẹlu, ti nfi ìwà-ipá on ẹ̀tan kún ile oluwa wọn. 10 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ohùn ẹkún yio ti ihà bodè-ẹja wá, ati hihu lati ihà keji wá, ati iro nla lati oke-kékèké wọnni wá. 11 Hu, ẹnyin ara Maktẹsi, nitoripe gbogbo enia oniṣòwo li a ti ke lu ilẹ; gbogbo awọn ẹniti o nrù fàdakà li a ke kuro. 12 Yio si ṣe li akokò na, li emi o fi fitilà wá Jerusalemu kiri, emi o si bẹ̀ awọn enia ti o silẹ sinu gẹ̀dẹgẹdẹ̀ wọn wò: awọn ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹ̃ni kì yio ṣe buburu. 13 Nitorina ogun wọn o di ikógun, ati ilẹ wọn yio di ahoro: nwọn o kọ́ ile pẹlu, ṣugbọn nwọn kì yio gbe inu wọn, nwọn o si gbìn ọgbà àjara, ṣugbọn nwọn kì yio mu ọti-waini inu rẹ̀. 14 Ọjọ nla Oluwa kù si dẹ̀dẹ, o kù si dẹ̀dẹ̀, o si nyara kánkan, ani ohùn ọjọ Oluwa: alagbara ọkunrin yio sọkun kikorò nibẹ̀. 15 Ọjọ na ọjọ ibinu ni, ọjọ iyọnu, ati ipọnju, ọjọ ofò ati idahoro, ọjọ okùnkun ọti okùdu, ọjọ kũku ati okunkun biribiri, 16 Ọjọ ipè ati idagirì si ilu olodi wọnni ati si iṣọ giga wọnni. 17 Emi o si mu ipọnju wá bá enia, ti nwọn o ma rìn bi afọju, nitori nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa: ẹjẹ̀ wọn li a o si tú jade bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ. 18 Fàdakà wọn tabi wurà wọn kì yio lè gbà wọn li ọjọ ìbinu Oluwa: ṣugbọn gbogbo ilẹ̀ na li a o fi iná ijowu rẹ̀ parun: nitori on o fi iyara mu gbogbo awọn ti ngbe ilẹ na kuro.

Sefaniah 2

Ìpè sí Ìrònúpìwàdà

1 Ẹ kó ara nyin jọ pọ̀, ani, ẹ kójọ pọ̀ orilẹ-ède ti kò nani; 2 Ki a to pa aṣẹ na, ki ọjọ na to kọja bi iyàngbò, ki gbigboná ibinu Oluwa to de ba nyin, ki ọjọ ibinu Oluwa ki o to de ba nyin. 3 Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹnyin ọlọkàn tutù aiye, ti nṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa-pẹ̀lẹ: boya a o pa nyin mọ li ọjọ ibinu Oluwa.

Ìparun tí Yóo Dé Bá Àwọn Ìlú tí Wọ́n Yí Israẹli Ká

4 Nitoripe a o kọ̀ Gasa silẹ, Aṣkeloni yio si dahoro: nwọn o le Aṣdodu jade li ọsangangan, a o si fà Ekronu tu kuro. 5 Egbe ni fun awọn ẹniti ngbe agbègbe okun, orilẹ-ède awọn ara Kereti! ọ̀rọ Oluwa dojukọ nyin; iwọ Kenaani, ilẹ awọn ara Filistia, emi o tilẹ pa ọ run, ti ẹnikan kì yio gbe ibẹ̀ mọ. 6 Agbègbe okun yio si jẹ ibujoko ati agọ fun awọn olùṣọ agùtan, ati agbo fun agbo-ẹran. 7 Agbègbe na yio si wà fun iyokù ile Juda; nwọn o jẹ̀ li ori wọn: ni ile Aṣkeloni wọnni ni nwọn o dùbulẹ li aṣãlẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbèkun wọn padà kuro. 8 Emi ti gbọ́ ẹgàn Moabu, ati ẹlẹyà awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti kẹgàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbe ara wọn ga si agbègbe wọn. 9 Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn. 10 Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoripe nwọn ti kẹgàn, nwọn si ti gbe ara wọn ga si enia Oluwa awọn ọmọ-ogun. 11 Oluwa yio jẹ ibẹ̀ru fun wọn: nitori on o mu ki gbogbo òriṣa ilẹ aiye ki o rù; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ̀ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi. 12 Ẹnyin ara Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin. 13 On o si nà ọwọ́ rẹ̀ si ihà ariwa, yio si pa Assiria run; yio si sọ Ninefe di ahoro, ati di gbigbẹ bi aginjù. 14 Agbo-ẹran yio si dùbulẹ li ãrin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ède: ati ẹiyẹ òfu ati õrẹ̀ yio ma gbe atẹrigbà rẹ̀, ohùn wọn yio kọrin li oju fèrese; idahoro yio wà ninu iloro: nitoriti on o ṣi iṣẹ kedari silẹ. 15 Eyi ni ilu alayọ̀ na ti o ti joko lainani ti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ni, kò si si ẹnikan ti mbẹ lẹhìn mi: on ha ti ṣe di ahoro bayi, ibùgbe fun ẹranko lati dubulẹ si! olukuluku ẹniti o ba kọja lọdọ rẹ̀ yio pòṣe yio si mì ọwọ́ rẹ̀.

Sefaniah 3

Ẹ̀ṣẹ̀ Jerusalẹmu ati Ìràpadà Rẹ̀

1 EGBE ni fun ọlọ̀tẹ ati alaimọ́, fun ilu aninilara nì. 2 On kò fetisi ohùn na; on kò gba ẹkọ́; on kò gbẹkẹ̀le Oluwa; on kò sunmọ ọdọ Ọlọrun rẹ̀. 3 Awọn olori rẹ̀ ti o wà lãrin rẹ̀ kiniun ti nke ramùramù ni nwọn; awọn onidajọ rẹ̀ ikõkò aṣãlẹ ni nwọn; nwọn kò sán egungun titi di owurọ̀. 4 Awọn woli rẹ̀ gberaga, nwọn si jẹ ẹlẹtàn enia: awọn alufa rẹ̀ ti ba ibi mimọ́ jẹ: nwọn ti rú ofin. 5 Oluwa li olõtọ lãrin rẹ̀, kì yio ṣe buburu: li orowurọ̀ li o nmu idajọ rẹ̀ wá si imọlẹ, kì itase; ṣugbọn awọn alaiṣõtọ kò mọ itìju. 6 Mo ti ke awọn orilẹ-ède kuro; ile giga wọn dahoro; mo sọ ita wọnni di ofo, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja ihà ibẹ̀: a pa ilu wọnni run, tobẹ̃ ti kò si enia kan, ti kò si ẹniti ngbe ibẹ̀. 7 Emi wipe, Lõtọ iwọ o bẹ̀ru mi, iwọ o gba ẹkọ́; bẹ̃ni a kì ba ti ke ibujoko wọn kuro, bi o ti wù ki mo jẹ wọn ni iyà to: ṣugbọn nwọn dide ni kùtukùtu, nwọn ba gbogbo iṣẹ wọn jẹ. 8 Nitorina ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ na ti emi o dide si ohun-ọdẹ: nitori ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ède jọ, ki emi ki o le kó awọn ilẹ ọba jọ, lati dà irúnu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owu mi jẹ gbogbo aiye run. 9 Nitori nigbana li emi o yi ède mimọ́ si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma pè orukọ Oluwa, lati fi ọkàn kan sìn i. 10 Lati oke odò Etiopia awọn ẹlẹbẹ̀ mi, ani ọmọbinrin afunká mi, yio mu ọrẹ mi wá. 11 Li ọjọ na ni iwọ kì yio tijú, nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti dẹṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu awọn ti nyọ̀ ninu igberaga rẹ kuro lãrin rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ li oke mimọ́ mi. 12 Emi o fi awọn otòṣi ati talakà enia silẹ pẹlu lãrin rẹ, nwọn o si gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa. 13 Awọn iyokù Israeli kì yio hùwa ibi, bẹ̃ni nwọn kì yio sọ̀rọ eke, bẹ̃ni a kì yio ri ahọn arekerekè li ẹnu wọn: ṣugbọn nwọn o jẹun nwọn o si dubulẹ, ẹnikan kì yio si dẹ̀ruba wọn.

Orin Ayọ̀

14 Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kigbe, iwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, ki inu rẹ ki o si dùn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu. 15 Oluwa ti mu idajọ rẹ wọnni kuro, o ti tì ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ. 16 Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀. 17 Oluwa Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; yio gbà ni là, yio yọ̀ li ori rẹ fun ayọ̀; yio simi ninu ifẹ rẹ̀, yio fi orin yọ̀ li ori rẹ. 18 Emi o kó awọn ti o banujẹ fun ajọ mimọ́ jọ awọn ti o jẹ tirẹ, fun awọn ti ẹgàn rẹ̀ jasi ẹrù. 19 Kiyesi i, nigbana li emi o ṣe awọn ti npọn ọ li oju: emi a gbà atiro là, emi o si ṣà ẹniti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyìn ati olokìki ni gbogbo ilẹ ti a ti gàn wọn. 20 Nigbana li emi o mu nyin padà wá, ani li akokò na li emi o ṣà nyin jọ: nitori emi o fi orukọ ati iyìn fun nyin lãrin gbogbo enia agbaiye, nigbati emi o yi igbèkun nyin padà li oju nyin, ni Oluwa wi.

Hagai 1

OLUWA pàṣẹ láti tún Tẹmpili Kọ́

1 LI ọdun keji Dariusi ọba, li oṣù kẹfa, li ọjọ ekini oṣù na, ọ̀rọ Oluwa wá, nipa ọwọ Hagai woli, sọdọ Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati sọdọ Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, wipe, 2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Awọn enia wọnyi nsọ pe, Akokò kò ti ide, akokò ti a ba fi kọ́ ile Oluwa. 3 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, wipe, 4 Akokò ha ni fun nyin, ẹnyin, lati ma gbe ile ọṣọ nyin, ṣugbọn ile yi wà li ahoro? 5 Njẹ nisisiyi bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ kiyesi ọ̀na nyin. 6 Ẹnyin ti fọ́n irugbin pupọ̀, ẹ si mu diẹ wá ile; ẹnyin njẹ, ṣugbọn ẹnyin kò yo: ẹnyin nmu, ṣugbọn kò tẹ nyin lọrun; ẹnyin mbora, ṣugbọn kò si ẹniti o gboná; ẹniti o si ngbowo ọ̀ya ńgbà a sinu ajadi àpo. 7 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ kiyesi ọ̀na nyin. 8 Ẹ gùn ori oke-nla lọ, ẹ si mu igi wá, ki ẹ si kọ́ ile na; inu mi yio si dùn si i, a o si yìn mi logo, li Oluwa wi. 9 Ẹnyin tí nreti ọ̀pọ, ṣugbọn kiyesi i, diẹ ni; nigbati ẹnyin si mu u wá ile, mo si fẹ ẹ danù. Nitori kini? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Nitori ti ile mi ti o dahoro; ti olukuluku nyin si nsare fun ile ara rẹ̀. 10 Nitorina ni a ṣe dá ìri ọrun duro lori nyin, a si da eso ilẹ duro. 11 Mo si ti pè ọdá sori ilẹ, ati sori oke-nla, ati sori ọkà ati sori ọti-waini titún, ati sori ororo, ati sori ohun ti ilẹ mu jade, ati sori enia, ati sori ẹran, ati sori gbogbo iṣẹ ọwọ ẹni.

Àwọn Eniyan náà gbọ́ràn sí Àṣẹ OLUWA

12 Nigbana ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, pẹlu gbogbo enia iyokù, gba ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ati ọ̀rọ Hagai woli, gẹgẹ bi Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a, awọn enia si bẹ̀ru niwaju Oluwa. 13 Nigbana ni Hagai iranṣẹ Oluwa jiṣẹ Oluwa fun awọn enia pe, Emi wà pẹlu nyin, li Oluwa wi. 14 Oluwa si rú ẹ̀mi Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda soke, ati ẹmi Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, ati ẹmi gbogbo awọn enia iyokù; nwọn si wá nwọn si ṣiṣẹ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun Ọlọrun wọn. 15 Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kẹfà, li ọdun keji Dariusi ọba.

Hagai 2

Ẹwà Tẹmpili Tuntun náà

1 LI oṣù keje, li ọjọ kọkanlelogun oṣù na, ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa ọwọ́ Hagai woli, wipe, 2 Sọ nisisiyi fun Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati fun Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa, ati fun awọn enia iyokù pe, 3 Tali o kù ninu nyin ti o ti ri ile yi li ogo rẹ̀ akọṣe? bawo li ẹnyin si ti ri i si nisisiyi? kò ha dàbi asan loju nyin bi a fi ṣe akawe rẹ̀? 4 Ṣugbọn nisisiyi mura giri, Iwọ Serubbabeli, li Oluwa wi, ki o si mura giri, Iwọ Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa; ẹ si mura giri gbogbo ẹnyin enia ilẹ na, li Oluwa wi, ki ẹ si ṣiṣẹ: nitori emi wà pẹlu nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 5 Gẹgẹ bi ọ̀rọ ti mo ba nyin dá majẹmu nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá, bẹ̃ni ẹmi mi wà lãrin nyin: ẹ máṣe bẹ̀ru. 6 Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Ẹ̃kan ṣa, nigbà diẹ si i, li emi o mì awọn ọrun, ati aiye, ati okun, ati iyàngbẹ ilẹ. 7 Emi o si mì gbogbo orilẹ-ède, ifẹ gbogbo orilẹ-ède yio si de: emi o si fi ogo kún ile yi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 8 Temi ni fàdakà, temi si ni wurà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 9 Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Wolii náà Lọ Bá Àwọn Àlùfáà Jíròrò

10 Li ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, pe, 11 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bère ofin lọwọ awọn alufa nisisiyi, pe, 12 Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ. 13 Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́. 14 Nigbana ni Hagai dahùn o si wipe, Bẹ̃ni enia wọnyi ri, bẹ̃ si ni orilẹ-ède yi ri niwaju mi, li Oluwa wi; bẹ̃ si li olukuluku iṣẹ ọwọ wọn; eyiti nwọn si fi rubọ nibẹ̀ jẹ alaimọ́.

OLUWA Ṣe Ìlérí Ibukun

15 Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ rò lati oni yi de atẹhìnwa, ki a to fi okuta kan le ori ekeji ninu tempili Oluwa; 16 Lati ọjọ wọnni wá, nigbati ẹnikan bã de ibi ile ogun, mẹwa pere ni: nigbati ẹnikan ba de ibi ifunti lati bã gbọ́n ãdọta akoto ninu ifunti na, ogún pere ni. 17 Mo fi ìrẹdanù ati imúwòdu ati yìnyin lù nyin ninu gbogbo iṣẹ ọwọ nyin: ṣugbọn ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. 18 Nisisiyi ẹ rò lati oni lọ de atẹhìnwa, lati ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, ani lati ọjọ ti a ti fi ipilẹ tempili Oluwa sọlẹ, ro o. 19 Eso ha wà ninu abà bi? lõtọ, àjara, ati igi òpọtọ, ati pomegranate, ati igi olifi, kò iti so sibẹ̀sibẹ̀: lati oni lọ li emi o bukún fun nyin.

Ìlérí OLUWA fún Serubabeli

20 Ọ̀rọ Oluwa si tún tọ̀ Hagai wá li ọjọ kẹrinlelogun oṣù na pe, 21 Sọ fun Serubbabeli, bãlẹ Juda, pe, emi o mì awọn ọrun ati aiye; 22 Emi o si bì itẹ awọn ijọba ṣubu, emi o si pa agbara ijọba keferi run; emi o si doju awọn kẹkẹ́ de, ati awọn ti o gùn wọn; ati ẹṣin ati awọn ẹlẹṣin yio wá ilẹ; olukuluku nipa idà arakunrin rẹ̀. 23 Li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o mu ọ, Iwọ Serubbabeli, iranṣẹ mi, ọmọ Ṣealtieli, li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di oruka edídi kan: nitoriti mo ti yàn ọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Sekariah 1

OLUWA Pe Àwọn Eniyan Rẹ̀ Pada Sọ́dọ̀

1 LI oṣù kẹjọ, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli, pe, 2 Oluwa ti binu pupọ̀ si awọn baba nyin. 3 Nitorina iwọ wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ yipadà si mi, emi o si yipadà si nyin, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 4 Ẹ má dàbi awọn baba nyin, awọn ti awọn woli iṣãju ti ké si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipadà nisisiyi kuro li ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu ìwa-buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò fetisi ti emi, ni Oluwa wi. 5 Awọn baba nyin, nibo ni nwọn wà? ati awọn woli, nwọn ha wà titi aiye? 6 Ṣugbọn ọ̀rọ mi ati ilàna mi, ti mo pa li aṣẹ fun awọn iranṣẹ mi woli, nwọn kò ha fi mu awọn baba nyin? nwọn si padà nwọn wipe, Gẹgẹ bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rò lati ṣe si wa, gẹgẹ bi ọ̀na wa, ati gẹgẹ bi iṣe wa, bẹ̃ni o ti ṣe si wa.

Ìran nípa Àwọn Ẹṣin

7 Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kọkanla, ti iṣe oṣù Sebati, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli wá, pe, 8 Mo ri li oru, si wò o, ọkunrin kan ngun ẹṣin pupa kan, on si duro lãrin awọn igi mirtili ti o wà ni ibi õji; lẹhìn rẹ̀ si li ẹṣin pupa, adíkalà, ati funfun gbe wà. 9 Nigbana ni mo wipe, Kini wọnyi oluwa mi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, emi o fi ohun ti wọnyi jẹ hàn ọ. 10 Ọkunrin ti o duro lãrin awọn igi mirtili si dahùn o si wipe, Wọnyi li awọn ti Oluwa ti rán lati ma rìn sokè sodò li aiye. 11 Nwọn si da angeli Oluwa ti o duro lãrin awọn igi mirtili na lohùn pe, Awa ti rìn sokè sodò já aiye, si kiyesi i, gbogbo aiye wà ni isimi, o si duro jẹ. 12 Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi? 13 Oluwa si fi ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ itùnu da angeli ti mba mi sọ̀rọ lohùn. 14 Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, Iwọ kigbe wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi nfi ijowu nla jowu fun Jerusalemu ati fun Sioni. 15 Emi si binu pupọ̀pupọ̀ si awọn orilẹ-ède ti o gbe jẹ: nitoripe emi ti binu diẹ, nwọn si ti kún buburu na lọwọ. 16 Nitorina bayi li Oluwa wi; mo padà tọ̀ Jerusalemu wá pẹlu ãnu; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, a o kọ ile mi sinu rẹ̀, a o si ta okùn kan jade sori Jerusalemu. 17 Ma ke sibẹ̀ pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; A o ma fi ire kún ilu-nla mi sibẹ̀; Oluwa yio si ma tù Sioni ninu sibẹ̀, yio si yàn Jerusalemu sibẹ̀.

Ìran nípa Àwọn Ìwo

18 Mo si gbe oju mi soke, mo si ri, si kiyesi i, iwo mẹrin. 19 Mo si sọ fun angeli ti o ba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi? O si da mi lohùn pe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda, Israeli, ati Jerusalemu ka. 20 Oluwa si fi gbẹnàgbẹnà mẹrin kan hàn mi. 21 Nigbana ni mo wipe, kini awọn wọnyi wá ṣe? O si sọ wipe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda ka, tobẹ̃ ti ẹnikẹni kò fi gbe ori rẹ̀ soke? ṣugbọn awọn wọnyi wá lati dẹruba wọn, lati le iwo awọn orilẹ-ède jade, ti nwọn gbe iwo wọn sori ilẹ Juda lati tu u ka.

Sekariah 2

Ìran nípa Okùn Ìwọ̀n

1 MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti on ti okùn-iwọ̀n lọwọ rẹ̀. 2 Mo si wipe, Nibo ni iwọ nlọ? o si wi fun mi pe, Lati wọ̀n Jerusalemu, lati ri iye ibú rẹ̀, ati iye gigùn rẹ̀. 3 Si kiyesi i, angeli ti o mba mi sọ̀rọ jade lọ, angeli miran si jade lọ ipade rẹ̀. 4 O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀: 5 Oluwa wipe, Emi o si jẹ odi iná fun u yika, emi o si jẹ ogo lãrin rẹ̀.

Pípe Àwọn tí A kó lẹ́rú pada Wálé

6 Ã! ã! sá kuro ni ilẹ ariwa, ni Oluwa wi; nitoripe bi afẹfẹ mẹrin ọrun ni mo tu nyin kakiri, ni Oluwa wi. 7 Sioni, gba ara rẹ là, iwọ ti o mba ọmọbinrin Babiloni gbe. 8 Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; lẹhìn ogo li o ti rán mi si awọn orilẹ-ède ti nkó nyin: nitori ẹniti o tọ́ nyin, o tọ́ ọmọ oju rẹ̀. 9 Nitori kiyesi i, emi o gbọ̀n ọwọ mi si ori wọn, nwọn o si jẹ ikogun fun iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi. 10 Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi. 11 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ. 12 Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu. 13 Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.

Sekariah 3

Ìran wolii náà nípa Olórí Àlùfáà

1 O sì fi Joṣua olori alufa hàn mi, o duro niwaju angeli Oluwa, Satani si duro lọwọ ọtun rẹ̀ lati kọju ijà si i. 2 Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, o ba ọ wi: igi iná kọ eyi ti a mu kuro ninu iná? 3 A si wọ̀ Joṣua li aṣọ ẽri, o si duro niwaju angeli na. 4 O si dahùn o wi fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Bọ aṣọ ẽri nì kuro li ara rẹ̀. O si wi fun u pe, Wò o, mo mu ki aiṣedẽde rẹ kuro lọdọ rẹ, emi o si wọ̀ ọ li aṣọ ẹyẹ. 5 Mo si wipe, Jẹ ki wọn fi lawàni mimọ́ wé e li ori. Nwọn si fi lawàni mimọ́ wé e lori, nwọn si fi aṣọ wọ̀ ọ. Angeli Oluwa si duro tì i. 6 Angeli Oluwa si tẹnu mọ fun Joṣua pe, 7 Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi. 8 Gbọ́ na, iwọ Joṣua olori alufa, iwọ, ati awọn ẹgbẹ́ rẹ ti o joko niwaju rẹ: nitori ẹni iyanu ni nwọn: nitori kiyesi i, emi o mu iranṣẹ mi, ẸKA, wá. 9 Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kalẹ niwaju Joṣua; lori okuta kan ni oju meje o wà: kiyesi i, emi o fin finfin rẹ̀, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si mu aiṣedẽde ilẹ na kuro ni ijọ kan. 10 Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, ni ọjọ na ni olukuluku yio pe ẹnikeji rẹ̀ sabẹ igi àjara ati sabẹ igi ọpọ̀tọ.

Sekariah 4

Ìran nípa Ọ̀pá Fìtílà

1 ANGELI ti o mba mi sọ̀rọ si tún de, o si ji mi, bi ọkunrin ti a ji lati oju orun rẹ̀, 2 O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Mo si wipe, mo wò, si kiyesi i, ọ̀pa fitilà ti gbogbo rẹ̀ jẹ wurà, pẹlu kòjo rẹ̀ lori rẹ̀, pẹlu fitilà meje rẹ̀ lori rẹ̀, ati àrọ meje fun fitilà mejeje, ti o wà lori rẹ̀: 3 Igi olifi meji si wà leti rẹ̀, ọkan li apa ọtun kòjo na, ati ekeji li apa osì rẹ̀. 4 Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ, pe, Kini wọnyi, Oluwa mi? 5 Angeli ti o mba mi sọ̀rọ dahùn o si wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, Nkò mọ̀, oluwa mi.

Ìlérí Ọlọrun fún Serubabeli

6 O si dahùn o si wi fun mi pe, Eyi ni ọ̀rọ Oluwa si Serubbabeli wipe, Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 7 Tani iwọ, Iwọ oke nla? iwọ o di pẹ̀tẹlẹ niwaju Serubbabeli: on o si fi ariwo mu okuta tenté ori rẹ̀ wá, yio ma kigbe wipe, Ore-ọfẹ, ore-ọfẹ si i. 8 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 9 Ọwọ Serubbabeli li o pilẹ ile yi; ọwọ rẹ̀ ni yio si pari rẹ̀; iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si nyin. 10 Ṣugbọn tani ha kẹgàn ọjọ ohun kekere? nitori nwọn o yọ̀, nwọn o si ri iwọ̀n lọwọ Serubbabeli pẹlu meje wọnni; awọn ni oju Oluwa, ti o nsare sihin sọhun ni gbogbo aiye. 11 Mo si dahun, mo si sọ fun u pe, Kini awọn igi olifi meji wọnyi jasi, ti o wà li apá ọtun fitilà ati li apá osì rẹ̀? 12 Mo si tún dahùn, mo si sọ fun u pe, Kini awọn ẹka meji igi olifi wọnyi jasi, ti ntú ororo wurà jade lori wọn lati inu ikòko wurà. 13 O si dahùn, o wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, N kò mọ̀, oluwa mi. 14 O si wipe, Awọn meji wọnyi ni awọn ti a fi ororo yàn, ti o duro tì Oluwa gbogbo aiye.

Sekariah 5

Ìran nípa Ìwé Kíká Tí Ó Ń Fò

1 NIGBANA ni mo yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, iwe-kiká ti nfò. 2 O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Emi si dahùn pe, mo ri iwe-kiká ti nfò; gigùn rẹ̀ jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹwa. 3 O si wi fun mi pe, Eyi ni ègun ti o jade lọ si gbogbo ilẹ aiye: nitori gbogbo awọn ti o ba jale ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀; gbogbo awọn ti o ba si bura ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀. 4 Emi o mu u jade, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, yio si wọ̀ inu ile olè lọ, ati inu ile ẹniti o ba fi orukọ mi bura eke: yio si wà li ãrin ile rẹ̀, yio si run u pẹlu igi ati okuta inu rẹ̀.

Ìran nípa Obinrin Tó Wà ninu Apẹ̀rẹ̀

5 Angeli ti mba mi sọ̀rọ si jade lọ, o si wi fun mi pe, Gbe oju rẹ si oke nisisiyi, ki o si wò nkan yi ti o jade lọ. 6 Mo si wipe, Kini nì? O si wipe, Eyi ni òṣuwọn efà ti o jade lọ. O si wipe, Eyi ni àworan ni gbogbo ilẹ aiye. 7 Si kiyesi i, a gbe talenti ojé soke: obinrin kan si niyi ti o joko si ãrin òṣuwọn efa. 8 O si wipe, Eyi ni ìwa-buburu. O si jù u si ãrin òṣuwọn efa: o si jù òṣuwọn ojé si ẹnu rẹ̀. 9 Mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, obinrin meji jade wá, ẹfũfu si wà ninu iyẹ wọn; nitori nwọn ni iyẹ bi iyẹ àkọ: nwọn si gbe òṣuwọn efa na de agbedemeji aiye on ọrun. 10 Mo si sọ fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ pe, Nibo ni awọn wọnyi ngbe òṣuwọn efa na lọ? 11 O si wi fun mi pe, Lati kọ́ ọ ni ile ni ilẹ Ṣinari: a o si fi idi rẹ̀ mulẹ, a o si fi ka ori ipilẹ rẹ̀ nibẹ̀.

Sekariah 6

Ìran nípa Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹrin

1 MO si yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, kẹkẹ́ mẹrin jade wá lati ãrin oke-nla meji; awọn oke-nla na si jẹ oke-nla idẹ. 2 Awọn ẹṣin pupa wà ni kẹkẹ́ ekini; ati awọn ẹṣin dudu ni kẹkẹ́ keji; 3 Ati awọn ẹṣin funfun ni kẹkẹ́ kẹta; ati awọn adikalà ati alagbara ẹṣin ni kẹkẹ́ kẹrin. 4 Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti mba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi, oluwa mi? 5 Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye. 6 Awọn ẹṣin dudu ti o wà ninu rẹ̀ jade lọ si ilẹ ariwa; awọn funfun si jade tẹ̀le wọn; awọn adíkalà si jade lọ si ihà ilẹ gusù. 7 Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye. 8 Nigbana ni on si kọ́ si mi, o si ba mi sọ̀rọ, wipe, Wò o, awọn wọnyi ti o lọ sihà ilẹ ariwa ti mu ẹmi mi parọrọ ni ilẹ ariwa.

Àṣẹ nípa ati Dé Joṣua ládé

9 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, 10 Mu ninu igbèkun, ninu awọn ti Heldai, ti Tobijah, ati ti Jedaiah, ti o ti Babiloni de, ki iwọ si wá li ọjọ kanna, ki o si wọ ile Josiah ọmọ Sefaniah lọ; 11 Ki o si mu fàdakà ati wurà, ki o si fi ṣe ade pupọ̀, ki o si gbe wọn kà ori Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa: 12 Si sọ fun u pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Wò ọkunrin na ti orukọ rẹ̀ njẹ ẸKA; yio si yọ ẹka lati abẹ rẹ̀ wá, yio si kọ́ tempili Oluwa; 13 On ni yio si kọ́ tempili Oluwa; on ni yio si rù ogo, yio si joko yio si jọba lori itẹ rẹ̀; on o si jẹ alufa lori itẹ̀ rẹ̀; ìmọ alafia yio si wà lãrin awọn mejeji. 14 Ade wọnni yio si wà fun Helemu, ati fun Tobijah, ati fun Jedaiah, ati fun Heni, ọmọ Sefaniah, fun iranti ni tempili Oluwa. 15 Awọn ti o jìna rére yio wá ikọle ni tempili Oluwa, ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rán mi si nyin. Yio si ri bẹ, bi ẹnyin o ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́ nitõtọ.

Sekariah 7

OLUWA Kọ Ààwẹ̀ Àgàbàgebè

1 O si ṣe li ọdun kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá ni ijọ kẹrin oṣù kẹsan, Kislefi; 2 Nigbati nwọn rán Ṣereṣeri ati Regemmeleki, ati awọn enia wọn si ile Ọlọrun lati wá oju rere Oluwa. 3 Ati lati bá awọn alufa ti o wà ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati awọn woli sọ̀rọ, wipe, Ki emi ha sọkun li oṣù karun, ki emi ya ara mi sọtọ, bi mo ti nṣe lati ọdun melo wonyi wá? 4 Nigbana li ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun tọ̀ mi wá wipe, 5 Sọ fun gbogbo awọn enia ilẹ na, ati fun awọn alufa, wipe, Nigbati ẹnyin gbawẹ̀ ti ẹ si ṣọ̀fọ li oṣù karun ati keje, ani fun ãdọrin ọdun wọnni, ẹnyin ha gbawẹ̀ si mi rara, ani si emi? 6 Nigbati ẹ si jẹ, ati nigbati ẹ mu, fun ara nyin ki ẹnyin ha jẹ, ati fun ara nyin ki ẹnyin ha mu? 7 Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ?

Àìgbọràn ló fa Ìkólọ-sóko-Ẹrú

8 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe, 9 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀. 10 Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀. 11 Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́. 12 Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá. 13 O si ṣe, gẹgẹ bi o ti kigbe, ti nwọn kò si fẹ igbọ́, bẹ̃ni nwọn kigbe, ti emi kò si fẹ igbọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 14 Mo si fi ãja tú wọn ka si gbogbo orilẹ-ède ti nwọn kò mọ̀. Ilẹ na si dahoro lẹhin wọn, ti ẹnikẹni kò là a kọja tabi ki o pada bọ̀: nwọn si sọ ilẹ ãyò na dahoro.

Sekariah 8

Ọlọrun ṣèlérí láti Dá Ibukun Jerusalẹmu Pada

1 Ọ̀RỌ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tun tọ̀ mi wá, wipe, 2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; owu nlanla ni mo jẹ fun Sioni, ikannu nlanla ni mo fi jowu fun u. 3 Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì. 4 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, arugbo ọkunrin ati arugbo obinrin, yio sa gbe igboro Jerusalemu, ati olukuluku ti on ti ọ̀pa li ọwọ rẹ̀ fun ogbó. 5 Igboro ilu yio si kún fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebinrin, ti nṣire ni ita wọn. 6 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, bi o ba ṣe iyanu li oju iyokù awọn enia yi li ọjọ wọnyi, iba jẹ iyanu li oju mi pẹlu bi? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 7 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Kiye si i, emi o gbà awọn enia mi kuro ni ilẹ ila-õrun, ati kuro ni ilẹ yama; 8 Emi o si mu wọn wá, nwọn o si ma gbe ãrin Jerusalemu: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, li otitọ, ati li ododo. 9 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Jẹ ki ọwọ nyin ki o le, ẹnyin ti ngbọ́ ọ̀rọ wọnyi li ọjọ wọnyi li ẹnu awọn woli ti o wà li ọjọ ti a fi ipilẹ ile Oluwa awọn ọmọ-ogun lelẹ, ki a ba le kọ́ tempili. 10 Nitori pe ṣãju ọjọ wọnni ọya enia kò to nkan, bẹni ọ̀ya ẹran pẹlu; bẹ̃ni kò si alafia fun ẹniti njade lọ, tabi ẹniti nwọle bọ̀, nitori ipọnju na: nitori mo doju gbogbo enia olukuluku kọ aladugbo rẹ̀. 11 Ṣugbọn nisisiyi emi kì yio ṣe si iyokù awọn enia yi gẹgẹ bi ti ìgba atijọ wọnni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 12 Nitori irugbin yio gbilẹ: àjara yio so eso rẹ̀, ilẹ yio si hù ọ̀pọlọpọ nkan rẹ̀ jade, awọn ọrun yio si mu irì wọn wá: emi o si mu ki awọn iyokù enia yi ni gbogbo nkan wọnyi. 13 Yio si ṣe, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ egún lãrin awọn keferi, ẹnyin ile Juda, ati ile Israeli, bẹ̃li emi o gbà nyin silẹ; ẹnyin o si jẹ ibukún: ẹ má bẹ̀ru, ṣugbọn jẹ ki ọwọ nyin ki o le. 14 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; gẹgẹ bi mo ti rò lati ṣẹ́ nyin niṣẹ, nigbati awọn baba nyin mu mi binu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi kò si ronupiwadà. 15 Bẹ̃li emi si ti rò ọjọ wọnyi lati ṣe rere fun Jerusalemu, ati fun ile Juda: ẹ má bẹ̀ru. 16 Wọnyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: Ẹ sọ̀rọ otitọ, olukuluku si ẹnikeji rẹ̀; ṣe idajọ tõtọ ati alafia ni bodè nyin wọnni. 17 Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o rò ibi li ọkàn rẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀; ẹ má fẹ ibura eke: nitori gbogbo wọnyi ni mo korira, li Oluwa wi. 18 Ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tọ̀ mi wá wipe, 19 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Ãwẹ̀ oṣù kẹrin, ati ti oṣù karun, ati ãwẹ̀ oṣù keje, ati ti ẹkẹwa, yio jẹ ayọ̀, ati didùn inu, ati apejọ ariya fun ile Juda; nitorina ẹ fẹ́ otitọ ati alafia. 20 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Awọn enia yio sa tún wá, ati ẹniti yio gbe ilu-nla pupọ. 21 Awọn ẹniti ngbe ilu-nla kan yio lọ si omiran, wipe, Ẹ jẹ ki a yára lọ igbadura niwaju Oluwa, ati lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun: emi pẹlu o si lọ. 22 Nitõtọ ọ̀pọlọpọ enia, ati awọn alagbara orilẹ-ède yio wá lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Jerusalemu; ati lati gbadura niwaju Oluwa. 23 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.

Sekariah 9

Ìdájọ́ lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Wọ́n Yí Israẹli Ká

1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa ni ilẹ Hadraki, Damasku ni yio si jẹ ibi isimi rẹ̀: nitori oju Oluwa mbẹ lara enia, ati lara gbogbo ẹ̀ya Israeli. 2 Ati Hamati pẹlu yio ṣe ãla rẹ̀: Tire ati Sidoni bi o tilẹ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi. 3 Tire si mọ odi lile fun ara rẹ̀, o si ko fàdakà jọ bi ekuru, ati wurà daradara bi ẹrẹ̀ ita. 4 Kiye si i, Oluwa yio tá a nù, yio si kọlu ipá rẹ̀ ninu okun; a o si fi iná jẹ ẹ run. 5 Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni. 6 Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro. 7 Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi. 8 Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri.

Ọba Tí Ń Bọ̀ Wá Jẹ

9 Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ. 10 Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.

Ìmúpadà Sípò Àwọn Eniyan Mi

11 Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi. 12 Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì. 13 Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara. 14 Oluwa yio si fi ara rẹ̀ hàn lori wọn, ọfà rẹ̀ yio si jade lọ bi mànamána: Oluwa Ọlọrun yio si fun ipè, yio si lọ ti on ti ãjà gusù. 15 Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dãbo bò wọn; nwọn o si jẹ ni run, nwọn o si tẹ̀ okuta kànna-kànna mọlẹ; nwọn o si mu, nwọn o si pariwo bi nipa ọti-waini; nwọn o si kún bi ọpọ́n, ati bi awọn igun pẹpẹ. 16 Oluwa Ọlọrun wọn yio si gbà wọn là li ọjọ na bi agbo enia rẹ̀: nitori nwọn o dabi awọn okuta ade, ti a gbe soke bi àmi lori ilẹ rẹ̀. 17 Nitori ore rẹ̀ ti tobi to, ẹwà rẹ̀ si ti pọ̀ to! ọkà yio mu ọdọmọkunrin darayá, ati ọti-waini titún yio mu awọn ọdọmọbinrin ṣe bẹ̃ pẹlu.

Sekariah 10

OLUWA Ṣèlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 Ẹ bère òjo nigba arọ̀kuro li ọwọ Oluwa; Oluwa yio kọ mànamána, yio si fi ọ̀pọ òjò fun wọn, fun olukulukù koriko ni pápa. 2 Nitori awọn oriṣa ti nsọ̀rọ asan, awọn alafọṣẹ si ti ri eké, nwọn si ti rọ́ alá eké; nwọn ntù ni ni inu lasan, nitorina nwọn ba ti wọn lọ bi ọwọ́ ẹran, a ṣẹ wọn niṣẹ, nitori darandaran kò si. 3 Ibinu mi ru si awọn darandaran, mo si jẹ awọn ewurẹ ni iyà; nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bẹ̀ agbo rẹ̀ ile Juda wò, o si fi wọn ṣe bi ẹṣin rẹ̀ daradara li ogun. 4 Lati ọdọ rẹ̀ ni igun ti jade wá, lati ọdọ rẹ̀ ni iṣo ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni ọrun ogun ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni awọn akoniṣiṣẹ gbogbo ti wá. 5 Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin. 6 Emi o si mu ile Juda le, emi o si gbà ile Josefu là, emi o si tún mu wọn joko; nitori mo ti ṣãnu fun wọn, nwọn o si dabi ẹnipe emi kò ti ta wọn nù: nitori emi ni Oluwa Ọlọrun wọn, emi o si gbọ́ ti wọn. 7 Efraimu yio si ṣe bi alagbara, ọkàn wọn yio si yọ̀ bi ẹnipe nipa ọti-waini: ani awọn ọmọ wọn yio ri i, nwọn o si yọ̀, inu wọn o si dùn si Oluwa. 8 Emi o kọ si wọn, emi o si ṣà wọn jọ; nitori emi ti rà wọn pada: nwọn o si rẹ̀ si i gẹgẹ bi wọn ti nrẹ̀ si i ri. 9 Emi o si gbìn wọn lãrin awọn enia: nwọn o si ranti mi ni ilẹ jijin; nwọn o si wà pẹlu awọn ọmọ wọn, nwọn o si tún pada. 10 Emi o si tún mu wọn pada kuro ni ilẹ Egipti pẹlu, emi o si ṣà wọn jọ kuro ni ilẹ Assiria: emi o si mu wọn wá si ilẹ Gileadi ati Lebanoni; a kì yio si ri àye fun wọn. 11 Yio si là okun wahala ja, yio si lù riru omi ninu okun, gbogbo ibu odò ni yio si gbẹ, a o si rẹ̀ igberaga Assiria silẹ, ọpa alade Egipti yio si lọ kuro. 12 Emi o si mu wọn le ninu Oluwa; nwọn o si rìn soke rìn sodò li orukọ rẹ̀, ni Oluwa wi.

Sekariah 11

Ìṣubú Àwọn Aninilára

1 ṢI ilẹkun rẹ wọnni silẹ, Iwọ Lebanoni, ki iná ba le jẹ igi kedari rẹ run. 2 Hu, igi firi; nitori igi kedari ṣubu; nitori ti a ba awọn alagbara jẹ: hu, ẹnyin igi oaku ti Baṣani, nitori a ke igbo ajara lulẹ. 3 Ohùn igbe awọn oluṣọ agutan; nitori ogo wọn bajẹ: ohùn bibu awọn ọmọ kiniun; nitori ogo Jordani bajẹ.

Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Meji

4 Bayi li Oluwa Ọlọrun mi wi; Bọ́ ọwọ́-ẹran abọ́pa. 5 Ti awọn oluwa wọn npa wọn, ti nwọn kò si kà ara wọn si pe nwọn jẹbi: ati awọn ti ntà wọn wipe, Ibukún ni fun Oluwa, nitoriti mo di ọlọrọ̀: awọn oluṣọ agutan wọn kò si ṣãnu wọn. 6 Nitori emi kì yio ṣãnu fun awọn ara ilẹ na mọ, li Oluwa wi; si kiye si i, emi o fi olukuluku enia le aladugbo rẹ̀ lọwọ, ati le ọwọ ọba rẹ̀: nwọn o si fọ́ ilẹ na, emi kì yio si gbà wọn lọwọ wọn. 7 Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na. 8 Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi. 9 Mo si wipe, emi kì yio bọ nyin: eyi ti nkú lọ, jẹ ki o kú; eyi ti a o ba si ke kuro, jẹ ki a ke e kuro; ki olukuluku ninu awọn iyokù jẹ ẹran-ara ẹnikeji rẹ̀. 10 Mo si mu ọpa mi, ani Ẹwà, mo si ṣẹ ẹ si meji, ki emi ba le dà majẹmu mi ti mo ti ba gbogbo awọn enia ni da. 11 O si dá li ọjọ na; bẹ̃ni awọn otoṣi ninu ọwọ́-ẹran nì ti o duro tì mi mọ̀ pe, ọ̀rọ Oluwa ni. 12 Mo si wi fun wọn pe, Bi o ba dara li oju nyin, ẹ fun mi ni owo-ọ̀ya mi: bi bẹ̃kọ, ẹ jọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn wọ̀n ọgbọ̀n owo fadakà fun iye mi. 13 Oluwa si wi fun mi pe, Sọ ọ si amọkòko: iye daradara na ti nwọn yọwó mi si. Mo si mu ọgbọ̀n owo fadakà na, mo si sọ wọn si amọkòko ni ile Oluwa. 14 Mo si ṣẹ ọpa mi keji, ani Amure, si meji, ki emi ki o le yà ibatan ti o wà lãrin Juda ati lãrin Israeli. 15 Oluwa si wi fun mi pe, Tún mu ohun-elò oluṣọ agutan aṣiwere kan sọdọ rẹ. 16 Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ. 17 Egbe ni fun oluṣọ agutan asan na ti o fi ọwọ́-ẹran silẹ! idà yio wà li apá rẹ̀, ati li oju ọ̀tun rẹ̀: apá rẹ̀ yio gbẹ patapata, oju ọ̀tun rẹ̀ yio si ṣõkùnkun biribiri.

Sekariah 12

Ìlérí Ìdáǹdè fún Jerusalẹmu

1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa fun Israeli, li Oluwa wi, ẹni ti o nnà awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ aiye sọlẹ, ti o si mọ ẹmi enia ti mbẹ ni inu rẹ̀. 2 Kiye si i, emi o sọ Jerusalemu di ago iwarìri si gbogbo enia yika, nigbati nwọn o do tì Juda ati Jerusalemu. 3 Li ọjọ na li emi o sọ Jerusalemu di ẹrù okuta fun gbogbo enia: gbogbo awọn ti o ba si fi dẹrù pa ara wọn li a o ke si wẹwẹ, bi gbogbo awọn orilẹ-ède aiye tilẹ ko ara wọn jọ si i. 4 Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o fi itagìri lù gbogbo ẹṣin, ati fi wère lu ẹniti ngùn u; emi o si ṣi oju mi si ile Juda, emi o si bu ifọju lù gbogbo ẹṣin ti enia na. 5 Ati awọn bãlẹ Juda yio si wi li ọkàn wọn pe, Awọn ara Jerusalemu li agbara mi nipa Oluwa Ọlọrun wọn. 6 Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu. 7 Oluwa pẹlu yio kọ́ tète gba agọ Juda là na, ki ogo ile Dafidi ati ogo awọn ara Jerusalemu ma bà gbe ara wọn ga si Juda. 8 Li ọjọ na li Oluwa yio dãbò bò awọn ti ngbe Jerusalemu; ẹniti o ba si ṣe ailera ninu wọn li ọjọ na yio dabi Dafidi; ile Dafidi yio si dabi Ọlọrun, bi angeli Oluwa niwaju wọn. 9 Yio si ṣe li ọjọ na, emi o wá lati pa gbogbo awọn orilẹ-ède run ti o wá kọjuja si Jerusalemu. 10 Emi o si tú ẹmi ore-ọfẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalemu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọ̀kọ, nwọn o si ma ṣọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi enia ti nṣọ̀fọ fun ọmọ ọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibanujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ̀. 11 Li ọjọ na li ọ̀fọ nlanlà yio wà ni Jerusalemu, gẹgẹ bi ọ̀fọ Hadadrimmoni li afonifoji Megiddoni. 12 Ilẹ na yio ṣọ̀fọ, idile idile lọtọ̀tọ; idile Dafidi lọ́tọ̀; ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Natani lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọtọ̀. 13 Idile Lefi lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Ṣimei lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀. 14 Gbogbo awọn idile ti o kù, idile idile lọtọ̀tọ, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀.

Sekariah 13

1 LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́. 2 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o ke orukọ awọn òriṣa kuro ni ilẹ na, a kì yio si ranti wọn mọ: ati pẹlu emi o mu awọn woli ati awọn ẹmi aimọ́ kọja kuro ni ilẹ na. 3 Yio si ṣe, nigbati ẹnikan yio sọtẹlẹ sibẹ̀, ni baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio wi fun u pe, Iwọ kì yio yè: nitori iwọ nsọ̀rọ eké li orukọ Oluwa: ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio gún u li agúnyọ nigbati o ba sọ̀tẹlẹ. 4 Yio si ṣe li ọjọ na, oju yio tì awọn woli olukulukù nitori iran rẹ̀, nigbati on ba ti sọtẹlẹ; bẹ̃ni nwọn kì yio si wọ̀ aṣọ onirun lati tan ni jẹ: 5 Ṣugbọn on o wipe, Emi kì iṣe woli, agbẹ̀ li emi; nitori enia li o ni mi bi iranṣẹ lati igbà ewe mi wá. 6 Ẹnikan o si wi fun u pe, Ọgbẹ́ kini wọnyi li ọwọ rẹ? On o si dahùn pe, Wọnyi ni a ti ṣá mi ni ile awọn ọrẹ́ mi.

Àṣẹ pé kí Wọ́n Pa Àwọn Olùṣọ́-Agutan Ọlọrun

7 Dide, iwọ idà, si olùṣọ-agùtan mi, ati si ẹniti iṣe ẹnikeji mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; kọlù olùṣọ-agùtan, awọn àgutan a si tuká: emi o si yi ọwọ mi si awọn kékèké. 8 Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li Oluwa wi, a o ké apá meji ninu rẹ̀ kuro yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rẹ̀. 9 Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi.

Sekariah 14

Jerusalẹmu ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 KIYESI i, ọjọ Oluwa mbọ̀, a o si pin ikogun rẹ lãrin rẹ. 2 Nitori emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si Jerusalemu fun ogun; a o si kó ilu na, a o si kó awọn ile, a o si bà awọn obinrin jẹ, abọ̀ ilu na yio lọ si igbèkun, a kì yio si ké iyokù awọn enia na kuro ni ilu na. 3 Nigbana ni Oluwa yio jade lọ, yio si ba awọn orilẹ-ède wọnni jà, gẹgẹ bi iti ijà li ọjọ ogun. 4 Ẹsẹ̀ rẹ̀ yio si duro li ọjọ na lori oke Olifi, ti o wà niwaju Jerusalemu ni ila-õrun, oke Olifi yio si là meji si ihà ila-õrun ati si ihà iwọ̀-õrun, afonifojì nlanla yio wà: idajì oke na yio si ṣi sihà ariwa, ati idajì rẹ̀ siha gusu. 5 Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀. 6 Yio si ṣe li ọjọ na, imọlẹ kì yio mọ́, bẹ̃ni kì yio ṣõkùnkun. 7 Ṣugbọn yio jẹ ọjọ kan mimọ̀ fun Oluwa, kì iṣe ọsan, kì iṣe oru; ṣugbọn yio ṣe pe, li aṣãlẹ imọlẹ yio wà. 8 Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃. 9 Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan. 10 A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba. 11 Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu. 12 Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn. 13 Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀. 14 Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ. 15 Bẹ̃ni àrun ẹṣin, ibãka, ràkumi, ati ti kẹtẹkẹtẹ, yio si wà, ati gbogbo ẹranko ti mbẹ ninu agọ wọnyi gẹgẹ bi àrun yi. 16 Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o kù ninu gbogbo awọn orilẹ-ède ti o dide si Jerusalemu yio ma goke lọ lọdọdun lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati lati pa àse agọ wọnni mọ. 17 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti kì yio goke wá ninu gbogbo idile aiye si Jerusalemu lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, fun wọn ni òjo kì yio rọ̀. 18 Bi idile Egipti kò ba si goke lọ, ti nwọn kò si wá, ti kò ni òjo; àrun na yio wà, ti Oluwa yio fi kọlù awọn keferi ti kò goke wá lati pa àse agọ na mọ. 19 Eyi ni yio si jẹ iyà Egipti, ati iyà gbogbo orilẹ-ède ti kò goke wá lati pa àse agọ mọ. 20 Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin; ati awọn ikòko ni ile Oluwa yio si dàbi awọn ọpọ́n wọnni niwaju pẹpẹ. 21 Nitõtọ, gbogbo ikòko ni Jerusalemu ati ni Juda yio jẹ mimọ́ si Oluwa awọn ọmọ-ogun: ati gbogbo awọn ti nrubọ yio wá, nwọn o si gbà ninu wọn, nwọn o si bọ̀ ninu rẹ̀: li ọjọ na ni ara Kenaani kì yio si si mọ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun.

Malaki 1

1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa si Israeli nipa ọwọ Malaki.

Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli

2 Emi ti fẹ nyin, li Oluwa wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kili o fẹ wa? Arakunrin Jakobu ki Esau iṣe? li Oluwa wi: bẹli emi sa fẹ Jakobu, 3 Mo si korira Esau, mo si sọ awọn oke-nla rẹ̀ ati ilẹ nini rẹ̀ di ahoro fun awọn dragoni aginjù. 4 Nitori Edomu wipe, A run wa tan, ṣugbọn awa o padà, a si kọ ibùgbe ahoro wọnni; bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Nwọn o kọ, ṣugbọn emi o wo lulẹ; Nwọn o si pe wọn ni, Agbègbe ìwa buburu, ati awọn enia ti Oluwa ni ikọnnu si titi lai. 5 Oju nyin o si ri, ẹnyin o si wipe, A o gbe Oluwa ga lati oke agbègbe Israeli wá.

OLUWA Bá Àwọn àlùfáàa Wí

6 Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọla mi ha da? bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀ru mi ha da? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin: Ẹnyin alufa, ti ngàn orukọ mi. Ẹnyin si wipe, Ninu kini awa fi kẹ́gàn orukọ rẹ? 7 Ẹnyin fi akarà aimọ́ rubọ lori pẹpẹ mi; ẹnyin si wipe, Ninu kini awa ti sọ ọ di aimọ́? Ninu eyi ti ẹnyin wipe, Tabili Oluwa di ohun ẹgàn. 8 Bi ẹnyin ba si fi eyi ti oju rẹ̀ fọ́ rubọ, ibi kọ́ eyini? bi ẹnyin ba si fi amúkun ati olokunrùn rubọ, ibi kọ́ eyini? mu u tọ bãlẹ rẹ lọ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi yio ha kà ọ si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 9 Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ bẹ̀ Ọlọrun ki o ba le ṣe ojurere si wa: lati ọwọ nyin li eyi ti wá: on o ha kà nyin si? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 10 Ta si ni ninu nyin ti yio se ilẹkun? bẹ̃li ẹnyin kò da iná asan lori pẹpẹ mi mọ. Emi kò ni inu-didùn si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bẹ̃li emi kì yio gba ọrẹ kan lọwọ nyin. 11 Nitori lati ilã-õrùn titi o si fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi; nibi gbogbo li a o si fi turàri jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mimọ́: nitori orukọ mi o tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 12 Nitori ẹnyin ti sọ ọ di aimọ́, ninu eyi ti ẹ wipe, Tabili Oluwa di aimọ́; ati eso rẹ̀, ani onjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gan. 13 Ẹnyin wi pẹlu pe, Wo o agara kili eyi! ẹnyin ṣitìmú si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o ya, ati arọ, ati olokunrùn wá; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin? li Oluwa wi. 14 Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtàn na, ti o ni akọ ninu ọwọ́-ẹran rẹ̀, ti o si ṣe ileri ti o si fi ohun abùku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla li emi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹ̀ru si li orukọ mi lãrin awọn keferi.

Malaki 2

1 NJẸ nisisiyi, ẹnyin alufa, ofin yi ni fun nyin. 2 Bi ẹnyin kì o ba gbọ́, ti ẹnyin kì o ba fi si aiya, lati fi ogo fun orukọ mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si rán egún si ori nyin, emi o si fi ibukun nyin ré, lõtọ mo ti fi ré na, nitori pe, ẹnyin kò fi i si ọkàn. 3 Wò o, emi o ba irugbìn nyin jẹ, emi o si fi igbẹ́ rẹ́ nyin loju, ani igbẹ́ asè ọ̀wọ nyin wọnni; a o si kó nyin lọ pẹlu rẹ̀. 4 Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li o ti rán ofin yi si nyin, ki majẹ̀mu mi le wà pẹlu Lefi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 5 Majẹmu mi ti iyè on alafia wà pẹlu rẹ̀; mo si fi wọn fun u, nitori bibẹ̀ru ti o bẹ̀ru mi, ti ẹ̀ru orukọ mi si bà a. 6 Ofin otitọ wà li ẹnu rẹ̀, a kò si ri ìwa-buburu li etè rẹ̀: o ba mi rìn li alafia ati ni ododo, o si yi ọ̀pọlọpọ kuro ninu ìwa-buburu. 7 Nitori ète alufa iba ma pa ìmọ mọ, ki nwọn ki o si ma wá ofin li ẹnu rẹ̀: nitori onṣẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun li on iṣe. 8 Ṣugbọn ẹnyin ti yapa kuro li ọ̀na na: ẹnyin ti mu ọ̀pọlọpọ kọsẹ ninu ofin; ẹnyin ti ba majẹmu Lefi jẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 9 Nitorina li emi pẹlu ṣe sọ nyin di ẹ̀gan, ati ẹni aikàsi niwaju gbogbo enia, niwọ̀n bi ẹnyin kò ti pa ọ̀na mi mọ, ti ẹnyin si ti nṣe ojusaju ninu ofin.

Aiṣootọ Àwọn Eniyan sí Ọlọrun

10 Baba kanna ki gbogbo wa ha ni? Ọlọrun kanna kó ha da wa bi? nitori kili awa ha ṣe nhùwa arekerekè olukuluku si arakunrin rẹ̀, nipa sisọ majẹmu awọn baba wa di alaimọ́. 11 Juda ti nhùwa arekerekè, a si ti nhùwa irira ni Israeli ati ni Jerusalemu: nitori Juda ti sọ ìwa mimọ́ Oluwa di alaimọ́, eyi ti o fẹ, o si ti gbe ọmọbinrin ọlọrun ajeji ni iyàwo. 12 Oluwa yio ke ọkunrin na ti o ṣe eyi kuro, olukọ ati ẹniti a nkọ, kuro ninu agọ Jakobu wọnni, ati ẹniti nrubọ ọrẹ si Oluwa awọn ọmọ-ogun. 13 Eyi li ẹnyin si tún ṣe, ẹnyin fi omije, ati ẹkún, ati igbe, bò pẹpẹ Oluwa mọlẹ, tobẹ̃ ti on kò fi kà ọrẹ nyin si mọ, tabi ki o fi inu-didùn gbà nkan lọwọ nyin. 14 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ. 15 On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀. 16 Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan.

Ọjọ́ Ìdájọ́ Súnmọ́lé

17 Ẹnyin ti fi ọ̀rọ nyin dá Oluwa li agara. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kini awa fi da a lagara? Nigbati ẹnyin wipe, Olukulùku ẹniti o ṣe ibi, rere ni niwaju Oluwa, inu rẹ̀ si dùn si wọn; tabi, nibo ni Ọlọrun idajọ gbe wà?

Malaki 3

1 KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 2 Ṣugbọn tali o le gbà ọjọ wíwa rẹ̀? tani yio si duro nigbati o ba fi ara hàn? nitori on dabi iná ẹniti ndà fadakà, ati bi ọṣẹ afọṣọ: 3 On o si joko bi ẹniti nyọ́, ti o si ndà fadakà: yio si ṣe awọn ọmọ Lefi mọ́, yio si yọ́ wọn bi wurà on fadakà, ki nwọn ki o le mu ọrẹ ododo wá fun Oluwa. 4 Nigbana ni ọrẹ Juda ati ti Jerusalemu yio wù Oluwa, gẹgẹ bi ti ọjọ igbãni, ati gẹgẹ bi ọdun atijọ. 5 Emi o si sunmọ nyin fun idajọ, emi o si ṣe ẹlẹri yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura eké, ati awọn ti o ni alagbaṣe lara ninu ọyà rẹ̀, ati opo, ati alainibaba, ati si ẹniti o nrẹ́ alejo jẹ, ti nwọn kò si bẹ̀ru mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Sísan ìdámẹ́wàá

6 Nitori Emi li Oluwa, Emi kò yipada; nitorina li a kò ṣe run ẹnyin ọmọ Jakobu. 7 Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada? 8 Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ. 9 Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi. 10 Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹ̃ ti ki yio si aye to lati gbà a. 11 Emi o si ba ajẹnirun wi nitori nyin, on kì o si run eso ilẹ nyin, bẹ̃ni àjara nyin kì o rẹ̀ dànu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 12 Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Ìlérí Àánú Tí Ọlọrun Ṣe

13 Ọ̀rọ nyin ti jẹ lile si mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ọ̀rọ kili awa sọ si ọ? 14 Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun? 15 Ṣugbọn nisisiyi awa pè agberaga li alabùkunfun; lõtọ awọn ti o nhùwa buburu npọ si i; lõtọ, awọn ti o dán Oluwa wò li a dá si. 16 Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀. 17 Nwọn o si jẹ temi ni ini kan, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li ọjọ na ti emi o dá; emi o si dá wọn si gẹgẹ bi enia iti ma dá ọmọ rẹ̀ si ti o nsìn i. 18 Nigbana li ẹnyin o yipada, ẹ o si mọ̀ iyatọ̀ lãrin olododo ati ẹni-buburu, lãrin ẹniti nsìn Ọlọrun, ati ẹniti kò sìn i.

Malaki 4

Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀

1 SA kiye si i, ọjọ na mbọ̀, ti yio ma jó bi iná ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yio dabi akékù koriko: ọjọ na ti mbọ̀ yio si jo wọn run, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti kì yio fi kù gbòngbo tabi ẹka fun wọn. 2 Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo. 3 Ẹnyin o si tẹ̀ awọn enia buburu mọlẹ: nitori nwọn o jasi ẽrú labẹ atẹlẹsẹ̀ nyin, li ọjọ na ti emi o dá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 4 Ẹ ranti ofin Mose iranṣẹ mi, eyi ti mo pa li aṣẹ fun u ni Horebu fun gbogbo Israeli, pẹlu aṣẹ ati idajọ wọnni. 5 Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà Oluwa, ati ọjọ ti o li ẹ̀ru to de: 6 Yio si pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ọkàn awọn ọmọ si ti awọn baba wọn, ki emi ki o má ba wá fi aiye gégun.

The New Testament of our Lord and Saviour Jesus Christ

Matteu 1

Ìran Jesu Kristi

1 IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu. 2 Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀; 3 Juda si bí Faresi ati Sara ti Tamari; Faresi si bí Esromu; Esromu si bí Aramu; 4 Aramu si bí Aminadabu; Aminadabu si bí Naaṣoni; Naaṣoni si bí Salmoni; 5 Salmoni si bí Boasi ti Rakabu; Boasi si bí Obedi ti Rutu; Obedi si bí Jesse; 6 Jesse si bí Dafidi ọba. Dafidi ọba si bí Solomoni lati ọdọ ẹniti o ti nṣe aya Uria; 7 Solomoni si bí Rehoboamu; Rehoboamu si bí Abia; Abia si bí Asa; 8 Asa si bí Jehosafati; Jehosafati si bí Joramu; Joramu si bí Osia; 9 Osia si bí Joatamu; Joatamu si bí Akasi; Akasi si bí Hesekiah; 10 Hesekiah si bí Manasse; Manasse si bí Amoni; Amoni si bí Josiah; 11 Josiah si bí Jekoniah ati awọn arakunrin rẹ̀, nigba ikolọ si Babiloni. 12 Lẹhin ikolọ si Babiloni ni Jekoniah bí Sealtieli; Sealtieli si bí Serubabeli; 13 Serubabeli si bí Abiudu; Abiudu si bí Eliakimu; Eliakimu si bí Asoru; 14 Asoru si bí Sadoku; Sadoku si bí Akimu; Akimu si bí Eliudu; 15 Eliudu si bí Eleasa; Eleasa si bí Matani; Matani si bí Jakọbu; 16 Jakọbu si bí Josefu ọkọ Maria, lati ọdọ ẹniti a bí Jesu, ti a npè ni Kristi. 17 Bẹ̃ni gbogbo iran lati Abrahamu wá de Dafidi jẹ iran mẹrinla; ati lati Dafidi wá de ikolọ si Babiloni jẹ iran mẹrinla; ati lati igba ikólọ si Babiloni de igba Kristi o jẹ iran mẹrinla.

Ìtàn Ìbí Jesu Kristi

18 Bi ibí Jesu Kristi ti ri niyi: li akokò ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josefu, ki nwọn to pade, a ri i, o lóyun lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá. 19 Josefu ọkọ rẹ̀, ti iṣe olõtọ enia, ko si fẹ dojutì i ni gbangba, o fẹ ikọ̀ ọ silẹ ni ìkọkọ. 20 Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angẹli Oluwa yọ si i li oju alá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má fòiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ ni. 21 Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn. 22 Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, 23 Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa. 24 Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ̀, o ṣe bi angẹli Oluwa ti wi fun u, o si mu aya rẹ̀ si ọdọ: 25 On ko si mọ̀ ọ titi o fi bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin: o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.

Matteu 2

Àwọn Amòye Wá Ọmọ náà Kàn

1 NIGBATI a si bí Jesu ni Betlehemu ti Judea, nigba aiye Herodu ọba, kiyesi, awọn amoye kan ti ìha ìla-õrùn wá si Jerusalemu, 2 Nwọn mbère wipe, Nibo li ẹniti a bí ti iṣe ọba awọn Ju wà? nitori awa ti ri irawọ rẹ̀ ni ìla-õrùn, awa si wá lati foribalẹ fun u. 3 Nigbati Herodu ọba si gbọ́, ara rẹ̀ kò lelẹ, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu pẹlu rẹ̀. 4 Nigbati o si pè gbogbo awọn olori alufa ati awọn akọwe awọn enia jọ, o bi wọn lẽre ibiti a o gbé bí Kristi. 5 Nwọn si wi fun u pe, Ni Betlehemu ti Judea ni: nitori bẹ̃li a kọwe rẹ̀ lati ọwọ́ woli nì wá, 6 Iwọ Betlehemu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israeli awọn enia mi. 7 Nigbana ni Herodu pè awọn amoye na si ìkọkọ, o sì bi wọn lẹsọlẹsọ akokò ti irawọ na hàn. 8 O si rán wọn lọ si Betlehemu, o wipe, Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu. 9 Nigbati nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ọba, nwọn lọ; si wò o, irawọ ti nwọn ti ri lati ìha ìla-õrùn wá, o ṣãju wọn, titi o fi wá iduro loke ibiti ọmọ-ọwọ na gbé wà. 10 Nigbati nwọn si ri irawọ na, nwọn yọ̀ ayọ nlanla. 11 Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia. 12 Bi Ọlọrun ti kìlọ fun wọn li oju alá pe, ki nwọn ki o máṣe pada tọ̀ Herodu lọ mọ́, nwọn gbà ọ̀na miran lọ si ilu wọn. 13 Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a. 14 Nigbati o si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀ li oru, o si lọ si Egipti; 15 O si wà nibẹ̀ titi o fi di igba ikú Herodu; ki eyi ti Oluwa wi lati ẹnu woli nì ki o le ṣẹ, pe, Ni Egipti ni mo ti pè ọmọ mi jade wá.

Hẹrọdu Ranṣẹ Lọ Pa Àwọn Ọmọde

16 Nigbati Herodu ri pe, on di ẹni itanjẹ lọdọ awọn amoye, o binu gidigidi, o si ranṣẹ, o si pa gbogbo awọn ọmọ ti o wà ni Betlehemu ati ni ẹkùn rẹ̀, lati awọn ọmọ ọdún meji jalẹ gẹgẹ bi akokò ti o ti bere lẹsọlẹsọ lọwọ awọn amoye na. 17 Nigbana li eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Jeremiah wa ṣẹ, pe, 18 Ni Rama ni a gbọ́ ohùn, ohùnréré, ati ẹkún, ati ọ̀fọ nla, Rakeli nsọkun awọn ọmọ rẹ̀ ko gbipẹ, nitoriti nwọn ko si.

Josẹfu Pada láti Ijipti

19 Nigbati Herodu si kú, kiyesi i, angẹli Oluwa kan yọ si Josefu li oju alá ni Egipti, 20 Wipe, Dide, mu ọmọ-ọwọ na, ati iya rẹ̀, ki o si lọ si ilẹ Israeli: nitori awọn ti nwá ẹmí ọmọ-ọwọ na lati pa ti kú. 21 O si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀, o si wá si ilẹ Israeli. 22 Ṣugbọn nigbati o gbọ́ pe Arkelau jọba ni Judea ni ipò Herodu baba rẹ̀, o bẹ̀ru lati lọ sibẹ̀; bi Ọlọrun si ti kìlọ fun u li oju alá, o yipada si apa Galili. 23 Nigbati o si wá, o joko ni ilu kan ti a npè ni Nasareti; ki eyi ti a ti sọ li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, A o pè e ni ará Nasareti.

Matteu 3

Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi

1 NI ijọ wọnni ni Johanu Baptisti wá, o nwasu ni ijù Judea, 2 O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀. 3 Nitori eyi li ẹniti woli Isaiah sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọ̀na rẹ̀ tọ́. 4 Aṣọ Johanu na si jẹ ti irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ si ẹ̀gbẹ rẹ̀; onjẹ rẹ̀ li ẽṣú ati oyin ìgan. 5 Nigbana li awọn ara Jerusalemu, ati gbogbo Judea, ati gbogbo ẹkùn apa Jordani yiká jade tọ̀ ọ wá, 6 A si mbaptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. 7 Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ awọn Farisi ati Sadusi wá si baptismu rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀? 8 Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada: 9 Ki ẹ má si ṣe rò ninu ara nyin, wipe, Awa ní Abrahamu ni baba; ki emi wi fun nyin, Ọlọrun le yọ ọmọ jade lati inu okuta wọnyi wá fun Abrahamu. 10 Ati nisisiyi pẹlu, a ti fi ãke le gbòngbo igi na; nitorina gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a o ke e lùlẹ, a o si wọ́ ọ jù sinu iná. 11 Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin. 12 Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, yio si gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, yio si kó alikama rẹ̀ sinu abà, ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.

Jesu Ṣe Ìrìbọmi

13 Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani sọdọ Johanu lati baptisi lọdọ rẹ̀. 14 Ṣugbọn Johanu kọ̀ fun u, wipe, Emi li a ba baptisi lọdọ rẹ, iwọ si tọ̀ mi wá? 15 Jesu si dahùn, o wi fun u pe, jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀. 16 Nigbati a si baptisi Jesu tan, o jade lẹsẹkanna lati inu omi wá; si wò o, ọrun ṣí silẹ fun u, o si ri Ẹmí Ọlọrun sọkalẹ bi adaba, o si bà le e: 17 Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Matteu 4

Satani Dán Jesu Wò

1 NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́ Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu. 2 Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a. 3 Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara. 4 Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá. 5 Nigbana ni Èṣu gbé e lọ soke si ilu mimọ́ nì, o gbé e le ṣonṣo tẹmpili, 6 O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. 7 Jesu si wi fun u pe, A tún kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò. 8 Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a; 9 O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi. 10 Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn. 11 Nigbana li Èṣu fi i silẹ lọ; si kiyesi i, awọn angẹli tọ̀ ọ wá, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u.

Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Galili

12 Nigbati Jesu gbọ́ pe, a fi Johanu le wọn lọwọ, o dide lọ si Galili; 13 Nigbati o si jade kuro ni Nasareti, o wá ijoko ni Kapernaumu, eyi ti o mbẹ leti okun li ẹkùn Sebuloni ati Neftalimu: 14 Ki eyi ti a wi lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, 15 Ilẹ Sebuloni ati ilẹ Neftalimu li ọ̀na okun, li oke Jordani, Galili awọn keferi; 16 Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun. 17 Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.

Jesu Pe Apẹja Mẹrin

18 Jesu nrin leti okun Galili, o ri awọn arakunrin meji, Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitori nwọn jẹ apẹja. 19 O si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia. 20 Nwọn si fi àwọn silẹ lojukanna, nwọn sì tọ̀ ọ lẹhin. 21 Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn. 22 Lojukanna nwọn si fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

Jesu Ń Ṣiṣẹ́ láàrin Ọpọlọpọ Eniyan

23 Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia. 24 Okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo Siria ká; nwọn si gbé awọn alaisàn ti o ni onirũru àrun ati irora wá sọdọ rẹ̀, ati awọn ti o li ẹmi èṣu, ati awọn ti o nsinwin, ati awọn ti o li ẹ̀gba; o si wò wọn sàn. 25 Ọpọlọpọ enia si tọ̀ ọ lẹhin lati Galili, ati Dekapoli, ati Jerusalemu, ati lati Judea wá, ati lati oke odò Jordani.

Matteu 5

Iwaasu Jesu lórí Òkè

1 NIGBATI o si ri ọ̀pọ enia, o gùn ori òke lọ: nigbati o si joko, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá. 2 O si yà ẹnu rẹ̀, o si kọ́ wọn, wipe,

Àwọn tí Ayọ̀ Wà fún

3 Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. 4 Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu. 5 Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye. 6 Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo. 7 Alabukún-fun li awọn alãnu: nitori nwọn ó ri ãnu gbà. 8 Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun. 9 Alabukún-fun li awọn onilaja: nitori ọmọ Ọlọrun ni a ó ma pè wọn. 10 Alabukúnfun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. 11 Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. 12 Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin.

Iyọ̀ ati Ìmọ́lẹ̀

13 Ẹnyin ni iyọ̀ aiye: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kini a o fi mu u dùn? kò nilari mọ́, bikoṣepe a dà a nù, ki o si di itẹmọlẹ li atẹlẹsẹ enia. 14 Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin. 15 Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi i sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ ninu ile. 16 Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.

Ẹ̀kọ́ nípa Òfin Mose

17 Ẹ máṣe rò pe, emi wá lati pa ofin tabi awọn wolĩ run: emi kò wá lati parun, bikoṣe lati muṣẹ. 18 Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin kì yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ̀ yio fi ṣẹ. 19 Ẹnikẹni ti o ba rú ọkan kikini ninu ofin wọnyi, ti o ba si nkọ́ awọn enia bẹ̃, on na li a o pè ni kikini ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nṣe wọn ti o ba si nkọ́ wọn, on na li a o pè ni ẹni-nla ni ijọba ọrun. 20 Nitori mo wi fun nyin, bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri.

Ẹ̀kọ́ nípa Ibinu

21 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ pania; ẹnikẹni ti o ba pania yio wà li ewu idajọ. 22 Ṣugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rẹ̀ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Alainilari, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu iná ọrun apadi. 23 Nitorina bi iwọ ba nmu ẹ̀bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, 24 Fi ẹ̀bun rẹ silẹ nibẹ̀ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ́ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn ẹ̀bun rẹ. 25 Ba ọtà rẹ rẹ́ kánkan nigbati iwọ wà li ọ̀na pẹlu rẹ̀; ki ọtá rẹ ki o má ba fi ọ le onidajọ lọwọ, onidajọ a si fi ọ le ẹ̀ṣọ lọwọ, a si gbè ọ sọ sinu tubu. 26 Lõtọ ni mo wi fun ọ, Iwọ kì yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.

Ẹ̀kọ́ nípa Àgbèrè

27 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga. 28 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀. 29 Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. 30 Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi.

Ẹ̀kọ́ nípa Kíkọ Aya Ẹni Sílẹ̀

31 A ti wi pẹlu pe, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, jẹ ki o fi iwe ìkọsilẹ le e lọwọ. 32 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe nitori àgbere, o mu u ṣe panṣaga; ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.

Ẹ̀kọ́ nípa Ìbúra

33 Ẹnyin ti gbọ́ ẹ̀wẹ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ kò gbọdọ bura, bikoṣepe ki iwọ ki o si mu ibura rẹ ṣẹ fun Oluwa. 34 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe bura rára, iba ṣe ifi ọrun bura, nitoripe itẹ́ Ọlọrun ni, 35 Tabi aiye, nitori apoti itisẹ rẹ̀ ni, tabi Jerusalemu, nitori ilu ọba nla ni. 36 Ki o maṣe fi ori rẹ bura, nitori iwọ ko le sọ irun kan di funfun tabi dudu. 37 Ṣugbọn jẹ ki ọ̀rọ nyin jẹ, Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ, bẹ̃kọ; nitoripe ohunkohun ti o ba jù wọnyi lọ, nipa ibi li o ti wá.

Ẹ̀kọ́ nípa Ẹ̀san Gbígbà

38 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Oju fun oju, ati ehín fun ehín: 39 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe kọ̀ ibi; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹrẹkẹ ọtún, yi ti òsi si i pẹlu. 40 Bi ẹnikan ba fẹ sùn ọ ni ile ẹjọ, ti o si gbà ọ li ẹ̀wu lọ, jọwọ agbáda rẹ fun u pẹlu. 41 Ẹnikẹni ti yio ba fi agbara mu ọ lọ si maili kan, bá a de meji. 42 Fifun ẹniti o bère lọwọ rẹ; ati lọdọ ẹniti o nfẹ win lọwọ rẹ, máṣe mu oju kuro.

Ìfẹ́ sí Ọ̀tá Ẹni

43 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ. 44 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; 45 Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ. 46 Nitori bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? 47 Bi ẹnyin ba si nkí kìki awọn arakunrin nyin, kili ẹ ṣe jù awọn ẹlomiran lọ? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? 48 Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé.

Matteu 6

Ẹ̀kọ́ nípa Ìtọrẹ Àánú

1 Ẹ kiyesi ara ki ẹ máṣe itọrẹ anu nyin niwaju enia, ki a ba le ri nyin: bi o ba ri bẹ̃, ẹnyin ko li ère lọdọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun. 2 Nitorina nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe fun fère niwaju rẹ, bi awọn agabagebe ti nṣe ni sinagogu ati ni ita, ki nwọn ki o le gbà iyìn enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. 3 Ṣugbọn nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ́ òsi rẹ ki o mọ̀ ohun ti ọwọ́ ọtún rẹ nṣe; 4 Ki itọrẹ ãnu rẹ ki o le wà ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ, on tikararẹ̀ yio san a fun ọ ni gbangba.

Ẹ̀kọ́ nípa Adura

5 Nigbati iwọ ba ngbadura, máṣe dabi awọn agabagebe; nitori nwọn fẹ ati mã duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọ̀na ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. 6 Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba. 7 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn. 8 Nitorina ki ẹnyin máṣe dabi wọn: Baba nyin sá mọ̀ ohun ti ẹnyin ṣe alaini, ki ẹ to bère lọwọ rẹ̀. 9 Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. 10 Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye. 11 Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. 12 Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa. 13 Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin. 14 Nitori bi ẹnyin ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin. 15 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ki yio si fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin.

Ẹ̀kọ́ nípa Ààwẹ̀ Gbígbà

16 Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. 17 Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ; 18 Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.

Ìṣúra ní Ọ̀run

19 Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale: 20 Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale. 21 Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.

Ìmọ́lẹ̀ Ara

22 Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ. 23 Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to!

Ọlọrun ati Ohun Ìní Eniyan

24 Ko si ẹniti o le sìn oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mammoni. 25 Nitorina mo wi fun nyin, Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ẹmí nyin ohun ti ẹ ó jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmí kò ha jù onjẹ lọ? tabi ara ni kò jù aṣọ lọ? 26 Ẹ sá wò ẹiyẹ oju ọrun; nwọn kì ifunrugbin, bẹ̃ni nwọn kì ikore, nwọn kì isi ikójọ sinu abà, ṣugbọn Baba nyin ti mbẹ li ọrun mbọ́ wọn. Ẹnyin kò ha san jù wọn lọ? 27 Tani ninu nyin nipa aniyàn ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? 28 Ẽṣe ti ẹnyin sì fi nṣe aniyan nitori aṣọ? Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ́, bi nwọn ti ndàgba; nwọn kì iṣiṣẹ, bẹ̃ni nwọn kì irànwu: 29 Mo si wi fun nyin pe, a ko ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ̀ to bi ọkan ninu wọnyi. 30 Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ bẹ̃, eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu iná lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin oni-kekere igbagbọ? 31 Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa? 32 Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi. 33 Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin. 34 Nitorina ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla; ọla ni yio ṣe aniyan ohun ara rẹ̀. Buburu ti õjọ to fun u.

Matteu 7

Ẹ̀kọ́ nípa Dídá Ẹlòmíràn Lẹ́jọ́

1 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, ki a ma bà da nyin li ẹjọ. 2 Nitori irú idajọ ti ẹnyin ba ṣe, on ni a o si ṣe fun nyin; irú òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o si fi wọ̀n fun nyin. 3 Etiṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ ko kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? 4 Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ. 5 Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro. 6 Ẹ máṣe fi ohun mimọ́ fun ajá, ki ẹ má si ṣe sọ ọṣọ́ nyin siwaju ẹlẹdẹ, ki nwọn má ba fi ẹsẹ tẹ̀ wọn mọlẹ, nwọn a si yipada ẹ̀wẹ, nwọn a si bù nyin ṣán.

Ẹ̀kọ́ nípa Ìtẹramọ́ Adura

7 Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin. 8 Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun. 9 Tabi ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rẹ̀ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u? 10 Tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò? 11 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀? 12 Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli.

Ẹnu-ọ̀nà tí Ó Fún

13 Ẹ ba ẹnu-ọ̀na hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọ̀na na, ati onibú li oju ọ̀na na ti o lọ si ibi iparun; òpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ̀ wọle. 14 Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i.

Èso Igi ni A Fi Ń Mọ Igi

15 Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. 16 Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn? 17 Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. 18 Igi rere ko le so eso buburu, bẹ̃ni igi buburu ko si le so eso rere. 19 Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná. 20 Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn.

Ìjẹ́wọ́ Ẹnu Kò Tó

21 Ki iṣe gbogbo ẹniti npè mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọ ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun. 22 Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla? 23 Nigbana li emi o si wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

Ìpìlẹ̀ Meji

24 Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata: 25 Òjo si rọ̀, ikún omi si dé, afẹfẹ si fẹ́ nwọn si bìlu ile na; ko si wó, nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori àpata. 26 Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin: 27 Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.

Àṣẹ Jesu

28 Nigbati o si ṣe ti Jesu pari gbogbo òrọ wọnyi tan, ẹnu yà gbogbo enia si ẹkọ́ rẹ̀: 29 Nitori o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, ki si iṣe bi awọn akọwe.

Matteu 8

Adẹ́tẹ̀ kan Rí Ìwòsàn

1 NIGBATI o ti ori òke sọkalẹ, ọ̀pọ enia ntọ̀ ọ lẹhin. 2 Si wò o, adẹtẹ̀ kan wá, o tẹriba fun u, o wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. 3 Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o wipe, Mo fẹ; iwọ di mimọ́. Lojukanna ẹ̀tẹ rẹ̀ si mọ́. 4 Jesu si wi fun u pe, Wò o, máṣe sọ fun ẹnikan; ṣugbọn mã ba ọ̀na rẹ lọ, fi ara rẹ hàn fun awọn alufa, ki o si fi ẹ̀bun ti Mose palaṣẹ li ẹrí fun wọn.

Jesu Wo Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọ̀gágun kan Sàn

5 Nigbati Jesu si wọ̀ Kapernaumu, balogun ọrún kan tọ̀ ọ wá, o mbẹ̀ ẹ, 6 O si nwipe, Oluwa, ọmọ-ọdọ mi dubulẹ arùn ẹ̀gba ni ile, ni irora pupọ̀. 7 Jesu si wi fun u pe, emi mbọ̀ wá mu u larada. 8 Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. 9 Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. 10 Nigbati Jesu gbọ́, ẹnu yà a, o si wi fun awọn ti o ntọ̀ ọ lẹhin pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi ko ri igbagbọ́ nla bi irú eyi ninu awọn enia Israeli. 11 Mo si wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrùn ati ìha íwọ-õrùn wá, nwọn a si ba Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun. 12 Ṣugbọn awọn ọmọ ilẹ-ọba li a o sọ sinu òkunkun lode, nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà. 13 Jesu si wi fun balogun ọrún na pe, Mã lọ, bi iwọ si ti gbagbọ́, bẹ̃ni ki o ri fun ọ. A si mu ọmọ-ọdọ rẹ̀ larada ni wakati kanna.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

14 Nigbati Jesu si wọ̀ ile Peteru lọ, o ri iya aya rẹ̀ dubulẹ àisan ibà. 15 O si fi ọwọ́ bà a li ọwọ́, ibà si fi i silẹ; on si dide, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. 16 Nigbati o si di aṣalẹ, nwọn gbe ọ̀pọlọpọ awọn ẹniti o ni ẹmi èṣu wá sọdọ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ rẹ̀ lé awọn ẹmi na jade, o si mu awọn olokunrun larada: 17 Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa.

Àwọn tí Ó Fẹ́ Tẹ̀lé Jesu

18 Nigbati Jesu ri ọ̀pọlọpọ enia lọdọ rẹ̀, o paṣẹ fun wọn lati lọ si apa keji adagun. 19 Akọwe kan si tọ̀ ọ wá, o wi fun u pe, Olukọni, emi ó mã tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ nlọ. 20 Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le. 21 Ekeji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinkú baba mi na. 22 Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Iwọ mã tọ̀ mi lẹhin, si jẹ ki awọn okú ki o mã sin okú ara wọn.

Jesu Bá Ìgbì Wí

23 Nigbati o si bọ si ọkọ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tẹ̀le e. 24 Si wò o, afẹfẹ nla dide ninu okun tobẹ̃ ti riru omi fi bò ọkọ̀ mọlẹ; ṣugbọn on sùn. 25 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn ji i, nwọn wipe, Oluwa, gbà wa, awa gbé. 26 O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe ojo bẹ̃, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Nigbana li o dide, o si ba afẹfẹ ati okun wi; idakẹrọrọ si de. 27 Ṣugbọn ẹnu yà awọn ọkunrin na, nwọn wipe, Irú enia wo li eyi, ti afẹfẹ ati omi okun gbọ tirẹ̀?

Jesu Wo Àwọn Ọkunrin Ẹlẹ́mìí Èṣù Ará Gadara Sàn

28 Nigbati o si de apa keji ni ilẹ awọn ara Gergesene, awọn ọkunrin meji ẹlẹmi èṣu pade rẹ̀, nwọn nti inu ibojì jade wá, nwọn rorò gidigidi tobẹ̃ ti ẹnikan ko le kọja li ọ̀na ibẹ̀. 29 Si wò o, nwọn kigbe soke wipe, Kini ṣe tawa tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun? iwọ wá lati da wa loro ki o to to akokò? 30 Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ ti njẹ mbẹ li ọ̀na jijìn si wọn. 31 Awọn ẹmi èṣu na si bẹ̀ ẹ, wipe, Bi iwọ ba lé wa jade, jẹ ki awa ki o lọ sinu agbo ẹlẹdẹ yi. 32 O si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ. Nigbati nwọn si jade, nwọn lọ sinu agbo ẹlẹdẹ na; si wò o, gbogbo agbo ẹlẹdẹ na rọ́ sinu okun li ogedengbe, nwọn si ṣegbé ninu omi. 33 Awọn ẹniti nṣọ wọn si sá, nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ si ilu, nwọn ròhin ohun gbogbo, ati ohun ti a ṣe fun awọn ẹlẹmi èṣu. 34 Si wò o, gbogbo ará ilu na si jade wá ipade Jesu; nigbati nwọn si ri i, nwọn bẹ̀ ẹ, ki o le lọ kuro li àgbegbe wọn.

Matteu 9

Jesu Wo Arọ kan Sàn

1 O si bọ sinu ọkọ̀, o rekọja, o si wá si ilu on tikararẹ̀. 2 Si kiyesi i, nwọn gbé ọkunrin kan ti o li ẹ̀gba wá sọdọ rẹ̀, o dubulẹ lori akete; nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọkunrin, tújuka, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. 3 Si kiyesi i, awọn ọkan ninu awọn akọwe nwi ninu ara wọn pe, ọkunrin yi nsọrọ-odi. 4 Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin? 5 Ewo li o rọrun ju, lati wipe, A dari ẹṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, ki o si mã rìn? 6 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o si wi fun alarun ẹ̀gba na pe,) Dide, si gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ. 7 O si dide, o si lọ ile rẹ̀. 8 Nigbati ijọ enia si ri i, ẹnu yà wọn, nwọn yìn Ọlọrun logo, ti o fi irú agbara bayi fun enia.

Jesu Pe Matiu

9 Bi Jesu si ti nrekọja lati ibẹ̀ lọ, o ri ọkunrin kan ti a npè ni Matiu joko ni bode; o sì wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin. 10 O si ṣe, bi Jesu ti joko tì onjẹ ninu ile, si kiyesi i, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá, nwọn si ba a joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 11 Nigbati awọn Farisi si ri i, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Olukọ nyin fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun pọ̀? 12 Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da. 13 Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

Ìbéèrè nípa Ààwẹ̀

14 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Johanu tọ̀ ọ wá wipe, Èṣe ti awa ati awọn Farisi fi ngbàwẹ nigbagbogbo, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ? 15 Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ. 16 Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju. 17 Bẹ̃ni ko si ẹniti ifi waini titun sinu ogbologbo igo-awọ; bi a ba ṣe bẹ̃, igo-awọ yio bẹ́, waini a si tú jade, igo-awọ a si ṣegbe; ṣugbọn waini titun ni nwọn ifi sinu igo-awọ titun, awọn mejeji a si ṣe dede.

Ọmọdebinrin Ìjòyè kan ati Obinrin Onísun Ẹ̀jẹ̀

18 Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè. 19 Jesu dide, o si ba a lọ, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 20 Si kiyesi i, obinrin kan ti o ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, o wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀. 21 Nitori o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ kàn aṣọ rẹ̀, ara mi ó da. 22 Nigbati Jesu si yi ara rẹ̀ pada ti o ri i, o wipe, Ọmọbinrin, tújuka, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. A si mu obinrin na larada ni wakati kanna. 23 Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo. 24 O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà. 25 Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide. 26 Okikí si kàn ká gbogbo ilẹ nã.

Jesu La Àwọn Afọ́jú Meji Lójú

27 Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. 28 Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa. 29 Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin. 30 Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀. 31 Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká.

Jesu Wo Odi kan Sàn

32 Bi nwọn ti njade lọ, wò o, nwọn mu ọkunrin odi kan tọ̀ ọ wá, ti o li ẹmi èṣu. 33 Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli. 34 Ṣugbọn awọn Farisi wipe, agbara olori awọn ẹmi èṣu li o fi lé awọn ẹmi èṣu jade.

Jesu Aláàánú

35 Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwãsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia. 36 Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti ãrẹ̀ mu wọn, nwọn, si tuká kiri bi awọn agutan ti ko li oluṣọ. 37 Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni ikorè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan; 38 Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikorè ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikorè rẹ̀.

Matteu 10

Jesu fún Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila Láṣẹ

1 NIGBATI o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila si ọdọ, o fi agbara fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́, lati ma lé wọn jade ati lati ṣe iwòsan gbogbo àrun ati gbogbo aisan. 2 Orukọ awọn aposteli mejila na ni wọnyi: Eyi ekini ni Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀; 3 Filippi, ati Bartolomeu; Tomasi, ati Matiu ti iṣe agbowode; Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Lebbeu, ẹniti a si npè ni Taddeu; 4 Simoni ara Kana, ati Judasi Iskariotu, ẹniti o fi i hàn.

Iṣẹ́ tí Jesu Rán Àwọn Aposteli Mejila

5 Awọn mejejila wọnyi ni Jesu rán lọ, o si paṣẹ fun wọn pe, Ẹ máṣe lọ si ọ̀na awọn keferi, ẹ má si ṣe wọ̀ ilu awọn ará Samaria; 6 Ṣugbọn ẹ kuku tọ̀ awọn agutan ile Israeli ti o nù lọ. 7 Bi ẹnyin ti nlọ, ẹ mã wasu, wipe, Ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ. 8 Ẹ mã ṣe dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, ẹ si jí awọn okú dide, ki ẹ si mã lé awọn ẹmi èṣu jade: ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni. 9 Ẹ máṣe pèse wura, tabi fadaka, tabi idẹ sinu aṣuwọn nyin; 10 Tabi àpo fun àjo nyin, ki ẹ máṣe mu ẹwu meji, tabi bata, tabi ọpá; onjẹ oniṣẹ yẹ fun u. 11 Ilu-kilu tabi iletò-kileto ti ẹnyin ba wọ̀, ẹ wá ẹniti o ba yẹ nibẹ ri, nibẹ̀ ni ki ẹ si gbé titi ẹnyin o fi kuro nibẹ̀. 12 Nigbati ẹnyin ba si wọ̀ ile kan, ẹ kí i. 13 Bi ile na ba si yẹ, ki alafia nyin ki o bà sori rẹ̀; ṣugbọn bi ko ba yẹ, ki alafia nyin ki o pada sọdọ nyin. 14 Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọ́ ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ile na tabi ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin silẹ. 15 Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu na lọ.

Inúnibíni tí Ó Ń Bọ̀

16 Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba. 17 Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn. 18 A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi. 19 Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna. 20 Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin. 21 Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn. 22 Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà. 23 Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de. 24 Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ. 25 O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀?

Ẹni tí Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù

26 Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀. 27 Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile. 28 Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi. 29 Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin. 30 Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. 31 Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.

Ìjẹ́wọ́ Kristi níwájú Eniyan

32 Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun. 33 Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.

Ọ̀rọ̀ nípa Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

34 Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà. 35 Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀. 36 Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ̀. 37 Ẹniti o ba fẹ baba tabi iya jù mi lọ, kò yẹ ni temi: ẹniti o ba si fẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù mi lọ, kò si yẹ ni temi. 38 Ẹniti kò ba si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin, kò yẹ ni temi. 39 Ẹniti o ba ri ẹmi rẹ̀, yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on ni yio si ri i.

Èrè

40 Ẹniti o ba gbà nyin, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi. 41 Ẹniti o ba gbà wolĩ li orukọ wolĩ, yio jẹ ère wolĩ; ẹniti o ba si gbà olododo li orukọ olododo yio jẹ ère olododo. 42 Ẹnikẹni ti o ba fi kìki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì o padanù ère rẹ̀.

Matteu 11

1 O si ṣe, nigbati Jesu pari aṣẹ rẹ̀ tan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila, o ti ibẹ̀ rekọja lati ma kọni, ati lati ma wasu ni ilu wọn gbogbo.

Johanu Onítẹ̀bọmi Ranṣẹ sí Jesu

2 Nigbati Johanu gburo iṣẹ Kristi ninu tubu, o rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji, 3 O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran? 4 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹnyin gbọ́, ti ẹ si ri fun Johanu: 5 Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi. 6 Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti kì yio ri ohun ikọsẹ ninu mi. 7 Nigbati nwọn si lọ, Jesu bẹrẹ si sọ fun awọn enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade lọ iwò ni ijù? Ifefe ti afẹfẹ nmì? 8 Ani kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ẹniti nwọ̀ aṣọ fẹlẹfẹlẹ mbẹ li afin ọba. 9 Ani kili ẹnyin jade lọ iṣe? lati lọ iwò wolĩ? Lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù wolĩ lọ. 10 Nitori eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. 11 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si ẹniti o ti idide jù Johanu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ. 12 Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a. 13 Nitori gbogbo awọn wolĩ ati ofin li o wi tẹlẹ ki Johanu ki o to de. 14 Bi ẹnyin o ba gbà a, eyi ni Elijah ti mbọ̀ wá. 15 Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. 16 Ṣugbọn kili emi iba fi iran yi wé? O dabi awọn ọmọ kekeke ti njoko li ọjà ti nwọn si nkọ si awọn ẹgbẹ wọn, 17 Ti nwọn si nwipe, Awa fun fère fun nyin ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun. 18 Nitori Johanu wá, kò jẹ, bẹ̃ni kò mu, nwọn si wipe, o li ẹmi èṣu. 19 Ọmọ-enia wá, o njẹ, o si nmu, nwọn wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn a dare fun ọgbọ́n lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ wá.

Ìdájọ́ lórí Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada

20 Nigbana li o bẹ̀rẹ si iba ilu wọnni wi, nibiti o gbé ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ agbara rẹ̀, nitoriti nwọn kò ronupiwada; 21 Egbé ni fun iwọ, Korasini! egbé ni fun iwọ, Betsaida! ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru. 22 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Tire pẹlu Sidoni li ọjọ idajọ jù fun ẹnyin lọ. 23 Ati iwọ Kapernaumu, a o ha gbé ọ ga soke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ si Ipo-oku: nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu rẹ ninu Sodomu, on iba wà titi di oni. 24 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu li ọjọ idajọ jù fun iwọ lọ.

Jesu ni Ìtura Àwọn Olùpọ́njú

25 Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́. 26 Gẹgẹ bẹ̃ na ni, Baba, nitori bẹ̀li o tọ́ li oju rẹ. 27 Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun. 28 Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ́, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin. 29 Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. 30 Nitori àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ.

Matteu 12

Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà ní Ọjọ́ Ìsinmi

1 LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ. 2 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi. 3 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀: 4 Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa? 5 Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi? 6 Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin. 7 Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi. 8 Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi.

Ọkunrin tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

9 Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn. 10 Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀. 11 O si wi fun wọn pe, ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke? 12 Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ? nitorina li o ṣe tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi. 13 Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ, on si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji.

Iranṣẹ Ọlọrun

14 Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.

Iranṣẹ Ọlọrun

15 Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada. 16 O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn: 17 Ki eyi ti a ti ẹnu wolĩ Isaiah wi ki o ba le ṣẹ, pe, 18 Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi. 19 On kì yio jà, kì yio si kigbe; bẹ̃li ẹnikẹni kì yio gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. 20 Iyè fifọ́ ni on kì yio ṣẹ́, owu fitila ti nru ẹ̃fin nì on kì yio si pa, titi yio fi mu idajọ dé iṣẹgun. 21 Orukọ rẹ̀ li awọn keferi yio ma gbẹkẹle.

Jesu ati Beelisebulu

22 Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran. 23 Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi? 24 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu. 25 Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro. 26 Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yapa si ara rẹ̀; ijọba rẹ̀ yio ha ṣe le duro? 27 Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina ni nwọn o fi ma ṣe onidajọ nyin. 28 Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin. 29 Tabi ẹnikan yio ti ṣe wọ̀ ile alagbara lọ, ki o si kó o li ẹrù, bikoṣepe o kọ́ dè alagbara na? nigbana ni yio si kó o ni ile. 30 Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka. 31 Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia. 32 Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀.

Igi ati Èso Rẹ̀

33 Sọ igi di rere, eso rẹ̀ a si di rere; tabi sọ igi di buburu, eso rẹ̀ a si di buburu: nitori nipa eso li ã fi mọ igi. 34 Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ. 35 Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá. 36 Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ. 37 Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi. 38 Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe ati Farisi dahùn wipe, Olukọni, awa nwá àmi lọdọ rẹ. 39 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Iran buburu ati iran panṣaga nwá àmi; kò si àmi ti a o fi fun u, bikoṣe àmi Jona wolĩ. 40 Nitori bi Jona ti gbé ọsán mẹta ati oru mẹta ninu ẹja; bẹ̃li Ọmọ-enia yio gbé ọsán mẹta on oru mẹta ni inu ilẹ. 41 Awọn ara Ninefe yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, nwọn, o si da a lẹbi: nitori nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Jona lọ mbẹ nihinyi. 42 Ọbabirin gusù yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, yio si da a lẹbi: nitori o ti ikangun aiye wá igbọ́ ọgbọ́n Solomoni; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.

Ẹ̀mí-Èṣù tún Pada sí Ilé Rẹ̀

43 Nigbati ẹmi aimọ́ kan ba jade kuro lara enia, a ma rìn kiri ni ibi gbigbẹ, a ma wá ibi isimi, kì si iri. 44 Nigbana ni o wipe, Emi o pada lọ si ile mi, nibiti mo gbé ti jade wá; nigbati o si de, o bá a, o ṣofo, a gbá a mọ́, a si ṣe e li ọṣọ. 45 Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu ara rẹ̀, ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn bọ si inu rẹ̀, nwọn si ngbé ibẹ̀; igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri fun iran buburu yi pẹlu.

Ìyá Jesu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

46 Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ. 47 Nigbana li ẹnikan wi fun u pe, Wo o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ba ọ sọ̀rọ. 48 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun ẹniti o sọ fun u pe, Tani iya mi? ati tani awọn arakunrin mi? 49 O si nà ọwọ́ rẹ̀ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Ẹ wò iya mi ati awọn arakunrin mi! 50 Nitori ẹnikẹni ti o ba nṣe ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.

Matteu 13

Òwe Afunrugbin

1 LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun. 2 Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun. 3 O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin; 4 Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. 5 Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ; 6 Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ. 7 Diẹ si bọ́ sãrin ẹ̀gún; nigbati ẹ̀gún si dàgba soke, o fun wọn pa. 8 Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n. 9 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́.

Ìdí tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti iwọ fi nfi owe ba wọn sọ̀rọ? 11 O si dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba ọrun, ṣugbọn awọn li a kò fifun. 12 Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a ó fifun, on o si ni li ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti ko ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni. 13 Nitorina ni mo ṣe nfi owe ba wọn sọ̀rọ; nitori ni riri, nwọn kò ri, ati ni gbigbọ, nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni kò yé wọn. 14 Si ara wọn ni ọrọ̀ Isaiah wolí si ti ṣẹ, ti o wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati riri ẹnyin o ri, ẹnyin kì yio si moye. 15 Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada. 16 Ṣugbọn ibukun ni fun oju nyin, nitoriti nwọn ri, ati fun etí nyin, nitoriti nwọn gbọ́. 17 Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ wolĩ ati olododo ni nfẹ ri ohun ti ẹnyin ri, nwọn kò si ri wọn; nwọn si nfẹ gbọ́ ohun ti ẹ gbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn.

Ìtumọ̀ Òwe Afunrugbin

18 Nitorina ẹ gbọ́ owe afunrugbin. 19 Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na. 20 Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan. 21 Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀. 22 Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso. 23 Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.

Òwe Èpò láàrin Ọkà

24 Owe miran li o pa fun wọn, wipe; Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀: 25 Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ. 26 Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu. 27 Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ bãle na tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun u pe, Oluwa, irugbin rere ki iwọ fún sinu oko rẹ? nibo li o ha ti li èpo buburu? 28 O si wi fun wọn pe, Ọtá li o ṣe eyi. Awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si bi i pe, Iwọ ha fẹ́ ki a lọ fà wọn tu kuro? 29 O si wipe, Bẹ̃kọ, nigbati ẹnyin ba ntu èpo kuro, ki ẹnyin ki o má bà tu alikama pẹlu wọn. 30 Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi.

Òwe Wóró Musitadi kan ati Ìwúkàrà

31 Owe miran li o pa fun wọn, wipe, Ijọba ọrun dabi wóro irugbin mustardi kan, eyiti ọkunrin kan mu ti o si gbìn sinu oko rẹ̀: 32 Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀. 33 Owe miran li o pa fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o sin sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ fi di wiwu.

Ìlò Òwe

34 Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu fi powe fun awọn ijọ enia; kò si ba wọn sọ̀rọ bikoṣe li owe: 35 Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá.

Ìtumọ̀ Òwe Èpò ninu Oko Ọkà

36 Nigbana ni Jesu rán ijọ enia lọ, o si wọ̀ ile; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, wipe, Sọ idi owe èpo ti oko fun wa. 37 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li ẹniti nfunrugbin rere; 38 Oko li aiye; irugbin rere li awọn ọmọ ijọba; èpo si li awọn ọmọ ẹni buburu ni; 39 Ọta ti o fún wọn li Èṣu; igbẹhin aiye ni ikorè; awọn angẹli si li awọn olukore. 40 Nitorina gẹgẹ bi a ti kó èpo jọ, ti a si fi iná sun wọn; bẹ̃ni yio ri ni igbẹhin aiye. 41 Ọmọ-enia yio rán awọn angẹli rẹ̀, nwọn o si kó gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ̀ ni ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ. 42 Yio si sọ wọn sinu iná ileru: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà. 43 Nigbana li awọn olododo yio ma ràn bi õrun ni ijọba Baba wọn. Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́.

Òwe Ìṣúra Iyebíye tí Wọ́n Fi Pamọ́

44 Ijọba ọrun si dabi iṣura ti a fi pamọ́ sinu oko, ti ọkunrin kan ri, ti o pa a mọ́; nitori ayọ̀ rẹ̀, o lọ, o si ta gbogbo ohun ti o ni, o si rà oko na.

Òwe Ìlẹ̀kẹ̀

45 Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi ọkunrin oniṣowo kan, ti nwá perli ti o dara: 46 Nigbati o ri perli olowo iyebiye kan, o lọ, o si tà gbogbo nkan ti o ni, o si rà a.

Òwe Àwọ̀n

47 Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi àwọn, ti a sọ sinu okun, ti o si kó onirũru ohun gbogbo. 48 Nigbati o kún, eyi ti nwọn fà soke, nwọn joko, nwọn si kó eyi ti o dara sinu agbọ̀n, ṣugbọn nwọn kó buburu danù. 49 Gẹgẹ bẹ̃ni yio si ri nigbẹhin aiye: awọn angẹli yio jade wá, nwọn o yà awọn enia buburu kuro ninu awọn olõtọ, 50 Nwọn o si sọ wọn sinu iná ileru; nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Nǹkan Titun ati Nǹkan Àtijọ́ ninu Àpò Ìṣúra

51 Jesu bi wọn pe, Gbogbo nkan wọnyi yé nyin bi? Nwọn wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa. 52 O si wi fun wọn pe, Nitorina ni olukuluku akọwe ti a kọ́ sipa ijọba ọrun ṣe dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle, ti o nmu ọtun ati ogbó nkan jade ninu iṣura rẹ̀.

Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu

53 Nigbati o ṣe, ti Jesu pari owe wọnyi tan, o ti ibẹ̀ lọ kuro. 54 Nigbati o si de ilu on tikalarẹ, o kọ́ wọn ninu sinagogu wọn, tobẹ̃ ti ẹnu yà gbogbo wọn, nwọn si wipe, Nibo li ọkunrin yi ti mu ọgbọ́n yi ati iṣẹ agbara wọnyi wá? 55 Ọmọ gbẹnagbẹna kọ yi? iya rẹ̀ kọ́ a npè ni Maria? ati awọn arakunrin rẹ̀ kọ́ Jakọbu, Jose, Simoni, ati Juda? 56 Ati awọn arabinrin rẹ̀, gbogbo wọn ki o mba wa gbé nihinyi? nibo li ọkunrin yi ti mu gbogbo nkan wọnyi wa? 57 Bẹ̃ni nwọn kọsẹ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Kò si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu ati ni ile on tikararẹ̀. 58 On kò si ṣe ọ̀pọ iṣẹ agbara nibẹ̀, nitori aigbagbọ́ wọn.

Matteu 14

Ikú Johanu Onítẹ̀bọmi

1 LI akokò na ni Herodu tetrarki gbọ́ okikí Jesu, 2 O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀. 3 Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀. 4 Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i. 5 Nigbati o si nfẹ pa a, o bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ. 6 Ṣugbọn nigbati a nṣe iranti ọjọ ibí Herodu, ọmọbinrin Herodia jó lãrin wọn, inu Herodu si dùn. 7 Nitorina li o ṣe fi ibura ṣe ileri lati fun u li ohunkohun ti o ba bère. 8 Ẹniti iya rẹ̀ ti kọ́ tẹlẹ ri, o wipe, Fun mi li ori Johanu Baptisti nihinyi ninu awopọkọ. 9 Inu ọba si bajẹ: ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati awọn ti o bá a joko tì onjẹ, o ni ki a fi fun u. 10 O si ranṣẹ lọ, o bẹ́ Johanu li ori ninu tubu. 11 A si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, a si fifun ọmọbinrin na; o si gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ. 12 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wá, nwọn gbé okú rẹ̀ sin, nwọn si lọ, nwọn si wi fun Jesu.

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

13 Nigbati Jesu si gbọ́, o dide kuro nibẹ̀, o ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù, on nikan; nigbati awọn enia si gbọ́, nwọn si ti ilu wọn rìn tọ̀ ọ li ẹsẹ. 14 Jesu jade lọ, o ri ọ̀pọlọpọ enia, inu rẹ̀ si yọ́ si wọn, o si ṣe dida arùn ara wọn. 15 Nigbati o di aṣalẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si kọja tan: rán ijọ enia lọ, ki nwọn ki o le lọ si iletò lọ irà onjẹ fun ara wọn. 16 Jesu si wi fun wọn pe, Nwọn kò ni ilọ; ẹ fun wọn li onjẹ. 17 Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun ati ẹja meji nihinyi. 18 O si wipe, Ẹ mu wọn fun mi wá nihinyi. 19 O si paṣẹ ki ijọ enia joko lori koriko, o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na; nigbati o gbé oju soke ọrun, o sure, o si bù u, o fi akara na fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia. 20 Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó; nwọn si ko ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n mejila kún. 21 Awọn ti o si jẹ ẹ to ìwọn ẹgbẹ̃dọgbọn ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde.

Jesu Rìn lórí Omi

22 Lojukanna Jesu si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o ṣiwaju rẹ̀ lọ si apakeji, nigbati on tú ijọ enia ká. 23 Nigbati o si tú ijọ enia ká tan, o gùn ori òke lọ, on nikan, lati gbadura: nigbati alẹ si lẹ, on nikan wà nibẹ̀. 24 Ṣugbọn nigbana li ọkọ̀ wà larin adagun, ti irumi ntì i siwa sẹhin: nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn. 25 Nigbati o di iṣọ kẹrin oru, Jesu tọ̀ wọn lọ, o nrìn lori okun. 26 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i ti o nrìn lori okun, ẹ̀ru bà wọn, nwọn wipe, Iwin ni; nwọn fi ibẹru kigbe soke. 27 Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. 28 Peteru si dá a lohùn, wipe, Oluwa, bi iwọ ba ni, paṣẹ ki emi tọ̀ ọ wá lori omi. 29 O si wipe, Wá. Nigbati Peteru sọkalẹ lati inu ọkọ̀ lọ, o rìn loju omi lati tọ̀ Jesu lọ. 30 Ṣugbọn nigbati o ri ti afẹfẹ le, ẹru ba a; o si bẹ̀rẹ si irì, o kigbe soke, wipe, Oluwa, gbà mi. 31 Lojukanna Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o dì i mu, o si wi fun u pe, Iwọ onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti iwọ fi nṣiyemeji? 32 Nigbati nwọn si bọ́ sinu ọkọ̀, afẹfẹ dá. 33 Nigbana li awọn ti mbẹ ninu ọkọ̀ wá, nwọn si fi ori balẹ fun u, wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun ni iwọ iṣe.

Jesu Wo Àwọn Aláìsàn Sàn ní Genesarẹti

34 Nigbati nwọn si rekọja si apakeji, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti. 35 Nigbati awọn enia ibẹ̀ si mọ̀ pe on ni, nwọn ranṣẹ lọ si gbogbo ilu na yiká, nwọn si gbé gbogbo awọn ọlọkunrùn tọ̀ ọ wá. 36 Nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn gbogbo awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, di alara dida ṣáṣá.

Matteu 15

Àṣà Ìbílẹ̀ Àwọn Juu

1 NIGBANA li awọn akọwe ati awọn Farisi ti Jerusalemu tọ̀ Jesu wá, wipe, 2 Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ fi nrú ofin atọwọdọwọ awọn alàgba? nitoriti nwọn kì iwẹ̀ ọwọ́ wọn nigbati nwọn ba njẹun. 3 Ṣugbọn o dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin pẹlu nfi ofin atọwọdọwọ nyin rú ofin Ọlọrun? 4 Nitori Ọlọrun ṣòfin, wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ati ẹniti o ba sọrọ baba ati iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀. 5 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẹnikẹni ti o ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, Ẹbùn li ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi, 6 Ti ko si bọ̀wọ fun baba tabi iya rẹ̀, o bọ́. Bẹ̃li ẹnyin sọ ofin Ọlọrun di asan nipa ofin atọwọdọwọ nyin. 7 Ẹnyin agabagebe, otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti nyin, wipe, 8 Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi. 9 Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ. 10 O si pè ijọ enia, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ki o si ye nyin; 11 Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́. 12 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ pe, awọn Farisi binu lẹhin igbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ yi? 13 O si dahùn, o wi fun wọn pe, Igikigi ti Baba mi ti mbẹ li ọrun kò ba gbìn, a o fà a tu kuro. 14 Ẹ jọwọ wọn si: afọju ti nfọ̀nahàn afọju ni nwọn. Bi afọju ba si nfọnahàn afọju, awọn mejeji ni yio ṣubu sinu ihò. 15 Nigbana ni Peteru dahùn o si wi fun u pe, Sọ itumọ owe yi fun wa. 16 Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ? 17 Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade? 18 Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́. 19 Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu; 20 Ohun wọnyi ni isọ enia di alaimọ́: ṣugbọn ki a jẹun li aiwẹwọ́ kò sọ enia di alaimọ́.

Igbagbọ Obinrin Ará Kenaani Kan

21 Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni. 22 Si wò o, obinrin kan ara Kenaani ti ẹkùn na wá, o si kigbe pè e, wipe, Oluwa, iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi; ọmọbinrin mi li ẹmi èṣu ndá lóró gidigidi. 23 Ṣugbọn kò si dá a lohùn ọrọ kan. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn bẹ̀ ẹ, wipe, Rán a lọ kuro, nitoriti o nkigbe tọ̀ wá lẹhin. 24 Ṣugbọn o dahùn wipe, A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israeli ti o nù. 25 Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ. 26 Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá. 27 O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ. 28 Nigbana ni Jesu dahùn o si wi fun u pe, Obinrin yi, igbagbọ́ nla ni tirẹ: ki o ri fun ọ gẹgẹ bi iwọ ti nfẹ. A si mu ọmọbinrin rẹ̀ larada ni wakati kanna.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

29 Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o wá si eti okun Galili, o gùn ori òke lọ, o si joko nibẹ̀. 30 Ọpọ enia si tọ̀ ọ wá ti awọn ti amukun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ awọn miran, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o si mu wọn larada: 31 Tobẹ̃, ti ẹnu yà ijọ enia na, nigbati nwọn ri ti odi nfọhùn, ti arọ ndi ọ̀tọtọ, ti amukun nrìn, ti afọju si nriran: nwọn si yìn Ọlọrun Israeli logo.

Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan

32 Jesu si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọdọ, o si wipe, Anu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn ko si li ohun ti nwọn o jẹ: emi kò si fẹ rán wọn lọ li ebi, ki ãrẹ̀ má bà mu wọn li ọ̀na. 33 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo li awa o ti ri akara to li aginjù, ti yio fi yó ọ̀pọ enia yi? 34 Jesu wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn wipe, Meje, pẹlu ẹja kekeke diẹ. 35 O si paṣẹ ki a mu ijọ enia joko ni ilẹ. 36 O si mu iṣu akara meje, ati ẹja na, o sure, o bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia. 37 Gbogbo nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n meje kún. 38 Awọn ti o jẹun to ẹgbaji ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde. 39 O si rán ijọ enia lọ; o si bọ́ sinu ọkọ̀, o lọ si ẹkùn Magdala.

Matteu 16

Àwọn Juu ń Fẹ́ Àmì

1 AWỌN Farisi pẹlu awọn Sadusi si wá, nwọn ndán a wò, nwọn si nfẹ ki o fi àmi hàn fun wọn lati ọrun wá. 2 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Nigbati ó ba di aṣalẹ, ẹnyin a wipe, Ọjọ ó dara: nitoriti oju ọrun pọ́n. 3 Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi? 4 Iran buburu ati panṣaga nfẹ àmi; a kì yio si fi àmi fun u, bikoṣe àmi ti Jona wolĩ. O si fi wọn silẹ, o kuro nibẹ.

Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Àwọn Sadusi

5 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si de apakeji, nwọn gbagbé lati mu akara lọwọ. 6 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹ si mã sọra niti iwukara awọn Farisi ati ti awọn Sadusi. 7 Nwọn si mbá ara wọn ṣaroye, wipe, Nitoriti awa ko mu akara lọwọ ni. 8 Nigbati Jesu si woye, o wi fun wọn pe, Ẹnyin onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti ẹnyin fi mba ara nyin ṣaroye, nitoriti ẹnyin ko mu akara lọwọ? 9 Kò iti yé nyin di isisiyi, ẹnyin kò si ranti iṣu akara marun ti ẹgbẹdọgbọn enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin si kójọ. 10 Ẹ kò si ranti iṣu akara meje ti ẹgbaji enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin kójọ? 11 Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin pe, emi kò ti itori akara sọ fun nyin pe, ẹ kiyesi ara nyin niti iwukara ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi. 12 Nigbana li o to yé wọn pe, ki iṣe iwukara ti akara li o wipe ki nwọn kiyesara rẹ̀, ṣugbọn ẹkọ́ ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni tí Jesu Í Ṣe

13 Nigbati Jesu de igberiko Kesarea Filippi, o bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre, wipe, Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe? 14 Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli. 15 O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? 16 Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe. 17 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun. 18 Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le; ẹnu-ọ̀na ipo-oku kì yio si le bori rẹ̀. 19 Emi ó si fun ọ ni kọkọrọ ijọba ọrun: ohunkohun ti iwọ ba dè li aiye, a o si dè e li ọrun: ohunkohun ti iwọ ba tú li aiye, a o si tú u li ọrun. 20 Nigbana li o kìlọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o màṣe sọ fun ẹnikan pe, on ni Kristi na.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

21 Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde. 22 Nigbana ni Peteru mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi pe, Ki a ma ri i, Oluwa, kì yio ri bẹ̃ fun ọ. 23 Ṣugbọn o yipada, o si wi fun Peteru pe, Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ̀ ni iwọ jẹ fun mi: iwọ ko rò ohun ti iṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi ti iṣe ti enia. 24 Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. 25 Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmi rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, yio ri i. 26 Nitoripe ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ̀ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ̀? 27 Nitori Ọmọ-enia yio wá ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigbana ni yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. 28 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri Ọmọ-enia ti yio ma bọ̀ ni ijọba rẹ̀.

Matteu 17

Jesu Para Dà

1 LẸHIN ijọ mẹfa Jesu mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin rẹ̀, o si mu wọn wá sori òke giga li apakan, 2 Ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn; oju rẹ̀ si nràn bi õrùn; aṣọ rẹ̀ si fún, o dabi imọle. 3 Si wo o, Mose ati Elijah yọ si wọn, nwọn mba a sọ̀rọ. 4 Peteru si dahùn, o si wi fun Jesu pe, Oluwa, o dara fun wa lati mã gbé ihin: bi iwọ ba fẹ, awa o pa agọ́ mẹta sihin; ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. 5 Bi o ti nwi lọwọ, wo o, awọsanma didán ṣiji bò wọn: si wo o, ohùn kan lati inu awọsanma wá, ti o wipe, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi; ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. 6 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́, nwọn da oju wọn bolẹ, ẹru si bà wọn gidigidi. 7 Jesu si wá, o fi ọwọ́ bà wọn, o si wipe, ẹ dide, ẹ má bẹ̀ru. 8 Nigbati nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn kò ri ẹnikan, bikoṣe Jesu nikan. 9 Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, Jesu kìlọ fun wọn pe, Ẹ máṣe sọ̀rọ iran na fun ẹnikan, titi Ọmọ-enia yio fi tun jinde kuro ninu okú. 10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe ha fi wipe, Elijah ni yio tètekọ de? 11 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Lõtọ ni, Elijah yio tètekọ de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò. 12 Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn kò si mọ̀ ọ, ṣugbọn nwọn ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i. Gẹgẹ bẹ̃ na pẹlu li Ọmọ-enia yio jìya pupọ̀ lọdọ wọn. 13 Nigbana li o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li ẹniti o nsọ̀rọ rẹ̀ fun wọn.

Jesu Wo Ọmọ tí Ó ní Ẹ̀mí Èṣù Sàn

14 Nigbati nwọn si de ọdọ ijọ enia, ọkunrin kan si tọ ọ wá, o kunlẹ fun u, o si wipe, 15 Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba pupọ sinu omi. 16 Mo si mu u tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada. 17 Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin. 18 Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna. 19 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade? 20 Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́ nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe. 21 Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

22 Nigbati nwọn mbẹ ni Galili, Jesu wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ: 23 Nwọn o si pa a, ni ijọ kẹta yio si jinde. Inu wọn si bajẹ gidigidi.

Jesu San Owó Tẹmpili

24 Nigbati nwọn de Kapernaumu, awọn ti ngbà owodè tọ̀ Peteru wá, wipe, olukọ nyin ki isan owodè? 25 O wipe, Bẹ̃ni. Nigbati o si wọ̀ ile, Jesu ṣiwaju rẹ̀, o bi i pe, Simoni, iwọ ti rò o si? lọwọ tali awọn ọba aiye ima gbà owodè? lọwọ awọn ọmọ wọn, tabi lọwọ awọn alejò? 26 Peteru wi fun u pe, Lọwọ awọn alejò. Jesu wi fun u pe, Njẹ awọn ọmọ bọ́. 27 Ṣugbọn ki a má bã bí wọn ninu, iwọ lọ si okun, ki o si sọ ìwọ si omi, ki o si mu ẹja ti o ba kọ́ fà soke; nigbati iwọ ba si yà a li ẹnu, iwọ o ri ṣekeli kan nibẹ̀: on ni ki o mu, ki o si fifun wọn fun temi ati tirẹ.

Matteu 18

Ta ní Ṣe Pataki Jùlọ ní Ìjọba Ọ̀run?

1 LAKOKÒ na li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Tali ẹniti o pọ̀ju ni ijọba ọrun? 2 Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn, 3 O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun. 4 Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun. 5 Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi,

Ẹ̀tàn sí Ẹ̀ṣẹ̀

6 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o ya fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si rì i si ibú omi okun. 7 Egbé ni fun aiye nitori ohun ikọsẹ̀! ohun ikọsẹ̀ ko le ṣe ki o ma de; ṣugbọn egbé ni fun oluwarẹ̀ na nipasẹ ẹniti ohun ikọsẹ̀ na ti wá! 8 Bi ọwọ́ rẹ tabi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ, tabí akesẹ lọ sinu ìye, jù ki o li ọwọ́ meji tabi ẹsẹ meji, ki a gbé ọ jù sinu iná ainipẹkun. 9 Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o lọ sinu ìye li olojukan, jù ki o li oju meji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apãdi.

Òwe Aguntan tí Ó Sọnù

10 Kiyesara ki ẹnyin má gàn ọkan ninu awọn kekeke wọnyi; nitori mo wi fun nyin pe, nigbagbogbo li ọrun li awọn angẹli wọn nwò oju Baba mi ti mbẹ li ọrun. 11 Nitori Ọmọ-enia wá lati gbà awọn ti o ti nù là. 12 Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi? 13 Njẹ bi o ba si ri i lõtọ ni mo wi fun nyin, o yọ̀ nitori agutan na yi, jù mọkandilọgọrun iyokù lọ ti ko nù. 14 Gẹgẹ bẹ̃ni kì iṣe ifẹ Baba nyin ti mbẹ li ọrun, ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ki o ṣegbé.

Arakunrin tí Ó Bá Dẹ́ṣẹ̀

15 Pẹlupẹlu bi arakunrin rẹ ba sẹ̀ ọ, lọ sọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ fun u ti iwọ tirẹ̀ meji: bi o ba gbọ́ tirẹ, iwọ mu arakunrin rẹ bọ̀ sipò. 16 Ṣugbọn bi kò ba gbọ́ tirẹ, nigbana ni ki iwọ ki o mu ẹnikan tabi meji pẹlu ara rẹ, ki gbogbo ọ̀rọ li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta ba le fi idi mulẹ. 17 Bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ wọn, wi fun ijọ enia Ọlọrun: bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ ti ijọ enia Ọlọrun, jẹ ki o dabi keferi si ọ ati agbowodè. 18 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba dè li aiye, a o dè e li ọrun, ohunkohun ti ẹnyin ba si tú li aiye, a o tú u li ọrun.

Adura Iṣọkan

19 Mo wi fun nyin ẹ̀wẹ pe, Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá. 20 Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kó ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ̀ li emi o wà li ãrin wọn.

Òwe Ẹrú tí Kò Ní Ẹ̀mí Ìdáríjì

21 Nigbana ni Peteru tọ̀ ọ wá, o wipe, Oluwa, nigba melo li arakunrin mi yio ṣẹ̀ mi, ti emi o si fijì i? titi di igba meje? 22 Jesu wi fun u pe, Emi kò wi fun ọ pe, Titi di igba meje, bikoṣe Titi di igba ãdọrin meje. 23 Nitorina ni ijọba ọrun fi dabi ọba kan ti nfẹ gbà ìṣirò lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. 24 Nigbati o bẹ̀rẹ si gbà iṣiro, a mu ọkan tọ̀ ọ wá, ti o jẹ ẹ li ẹgbãrun talenti. 25 Njẹ bi ko ti ni ohun ti yio fi san a, oluwa rẹ̀ paṣẹ pe ki a tà a, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ki a si san gbese na. 26 Nitorina li ọmọ-ọdọ na wolẹ o si tẹriba fun u, o nwipe, Oluwa, mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ. 27 Oluwa ọmọ-ọdọ na si ṣãnu fun u, o tú u silẹ, o fi gbese na jì i. 28 Ṣugbọn nigbati ọmọ-ọdọ na jade lọ, o si ri ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀, ti o jẹ ẹ li ọgọrun owo idẹ: o gbé ọwọ́ le e, o fún u li ọrùn, o wipe, San gbese ti iwọ jẹ mi. 29 Ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀ kunlẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ. 30 On kò si fẹ; o lọ, o gbé e sọ sinu tubu titi yio fi san gbese na. 31 Nigbati awọn iranṣẹ ẹgbẹ rẹ̀ ri eyi ti a ṣe, ãnu ṣe wọn gidigidi, nwọn lọ nwọn si sọ gbogbo ohun ti a ṣe fun oluwa wọn. 32 Nigbati oluwa rẹ̀ pè e tan, o wi fun u pe, A! iwọ iranṣẹ buburu yi, Mo fi gbogbo gbese nì jì ọ, nitoriti iwọ bẹ̀ mi: 33 Iwọ kì isi ṣãnu iranṣẹ ẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi mo ti ṣãnu fun ọ? 34 Oluwa rẹ̀ si binu, o fi i fun awọn onitubu, titi yio fi san gbogbo gbese eyi ti o jẹ ẹ. 35 Bẹ̃ na gẹgẹ ni Baba mi ti mbẹ li ọrun yio si ṣe fun nyin, bi olukuluku kò ba fi tọkàn-tọkan rẹ̀ dari ẹ̀ṣẹ arakunrin rẹ̀ jì i.

Matteu 19

Ẹ̀kọ́ nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn

1 O si ṣe, nigbati Jesu pari ọ̀rọ wọnyi tan, o kuro ni Galili, o si lọ si ẹkùn Judea li oke odò Jordani. 2 Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, o si mu wọn larada nibẹ̀. 3 Awọn Farisi si wá sọdọ rẹ̀, nwọn ndán a wò, nwọn si wi fun u pe, O ha tọ́ fun ọkunrin ki o kọ̀ aya rẹ̀ silẹ nitori ọ̀ran gbogbo? 4 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo, 5 O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan. 6 Nitorina nwọn ki iṣe meji mọ́ bikoṣe ara kan. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn. 7 Nwọn wi fun u pe, Ẽṣe ti Mose fi aṣẹ fun wa, wipe, ki a fi iwe ikọsilẹ fun u, ki a si kọ̀ ọ silẹ? 8 O wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin ni Mose ṣe jẹ fun nyin lati mã kọ̀ aya nyin silẹ, ṣugbọn lati igba àtetekọṣe wá kò ri bẹ̃. 9 Mo si wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣepe nitori àgbere, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. 10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Bi ọ̀ran ọkunrin ba ri bayi si aya rẹ̀, kò ṣànfani lati gbé iyawo. 11 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Gbogbo enia kò le gbà ọ̀rọ yi, bikoṣe awọn ẹniti a fi bùn. 12 Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a.

Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde

13 Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi. 14 Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun. 15 O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀.

Ìtàn Ọdọmọkunrin Ọlọ́rọ̀

16 Si kiyesi i, ẹnikan tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Olukọni rere, ohun rere kili emi o ṣe, ki emi ki o le ni ìye ainipẹkun? 17 O si wi fun u pe, Eṣe ti iwọ fi pè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun: ṣugbọn bi iwọ ba nfẹ wọ̀ ibi ìye, pa ofin mọ́. 18 O bi i lẽre pe, Ewo? Jesu wipe, Iwọ kò gbọdọ pa enia; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jale; Iwọ kò gbọdọ jẹri eke; 19 Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ. 20 Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù? 21 Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin. 22 Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀. 23 Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun. 24 Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. 25 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là? 26 Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe. 27 Nigbana ni Peteru dahùn, o si wi fun u pe, Wò o, awa ti fi gbogbo rẹ̀ silẹ, awa si ntọ̀ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni? 28 Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila. 29 Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun. 30 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

Matteu 20

Àwọn Òṣìṣẹ́ ninu Ọgbà Àjàrà

1 IJỌBA ọrun sá dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle ile, ti o jade ni kutukutu owurọ lati pè awọn alagbaṣe sinu ọgba ajara rẹ̀. 2 Nigbati o si ba awọn alagbaṣe pinnu rẹ̀ si owo idẹ kọkan li õjọ, o rán wọn lọ sinu ọgba ajara rẹ̀. 3 O si jade lakokò wakati ẹkẹta ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran, nwọn duro nibi ọja, 4 O si wi fun wọn pe; Ẹ lọ si ọgba ajara pẹlu, ohunkohun ti o ba tọ́ emi o fifun nyin. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ sibẹ̀. 5 O tún jade lọ lakokò wakati kẹfa ati kẹsan ọjọ, o si ṣe bẹ̃. 6 O si jade lọ lakokò wakati kọkanla ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran ti o duro, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe? 7 Nwọn wi fun u pe, Nitoriti kò si ẹni ti o fun wa li agbaṣe; O wi fun wọn pe, Ẹ lọ pẹlu sinu ọgba ajara; eyi ti o ba tọ́ li ẹnyin o ri gbà. 8 Nigbati o di oju alẹ oluwa ọgba ajara wi fun iriju rẹ̀ pe, Pè awọn alagbaṣe nì, ki o si fi owo agbaṣe wọn fun wọn, bẹ̀rẹ lati ẹni ikẹhin lọ si ti iṣaju. 9 Nigbati awọn ti a pè lakokò wakati kọkanla ọjọ de, gbogbo wọn gbà owo idẹ kọkan. 10 Ṣugbọn nigbati awọn ti o ti ṣaju de, nwọn ṣebi awọn o gbà jù bẹ̃ lọ; olukuluku wọn si gbà owo idẹ kọkan. 11 Nigbati nwọn gbà a tan, nwọn nkùn si bãle na, 12 Wipe, Awọn ará ikẹhin wọnyi ṣiṣẹ kìki wakati kan, iwọ si mu wọn bá wa dọgba, awa ti o ti rù ẹrù, ti a si faradà õru ọjọ. 13 O si da ọkan ninu wọn lohùn pe, Ọrẹ́, emi ko ṣìṣe si ọ: iwọ ki o ba mi pinnu rẹ̀ si owo idẹ kan li õjọ? 14 Gbà eyi ti iṣe tirẹ, ki o si ma ba tirẹ lọ: emi o si fifun ikẹhin yi, gẹgẹ bi mo ti fifun ọ. 15 Kò ha tọ́ ki emi ki o fi nkan ti iṣe ti emi ṣe bi o ti wù mi? oju rẹ korò nitoriti emi ṣe ẹni rere? 16 Bẹ̃li awọn ikẹhin yio di ti iwaju, awọn ẹni iwaju yio si di ti ikẹhin: nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

17 Jesu si ngoke lọ si Jerusalemu, o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila si apakan li ọ̀na, o si wi fun wọn pe, 18 Wò o, awa ngoke lọ si Jerusalemu; a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ, nwọn o si da a lẹbi ikú. 19 Nwọn o si fà a le awọn keferi lọwọ lati fi i ṣe ẹlẹyà, lati nà a, ati lati kàn a mọ agbelebu: ni ijọ kẹta yio si jinde.

Ìbéèrè Jakọbu ati Johanu

20 Nigbana ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọn ọmọ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o bẹ̀ ẹ, o si nfẹ ohun kan li ọwọ́ rẹ̀. 21 O si bi i pe, Kini iwọ nfẹ? O wi fun u pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ́ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ́ òsi ni ijọba rẹ. 22 Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e. 23 O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá. 24 Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́ ọ, nwọn binu si awọn arakunrin wọn mejeji. 25 Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹnyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a ma lò agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. 26 Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ̀ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin; 27 Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin: 28 Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.

Jesu La Ojú Afọ́jú Meji

29 Bi nwọn ti nti Jeriko jade, ọ̀pọ enia tọ̀ ọ lẹhin. 30 Si kiyesi i, awọn ọkunrin afọju meji joko leti ọ̀na, nigbati nwọn gbọ́ pe Jesu nrekọja, nwọn kigbe soke, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. 31 Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. 32 Jesu si dẹsẹ duro, o pè wọn, o si wipe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? 33 Nwọn wi fun u pe, Oluwa, ki oju wa ki o le là. 34 Bẹ̃ni Jesu ṣãnu fun wọn, o si fi ọwọ́ tọ́ wọn li oju: lọgan oju wọn si là, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

Matteu 21

Jesu Fi Ẹ̀yẹ Wọ Jerusalẹmu

1 NIGBATI nwọn sunmọ eti Jerusalemu, ti nwọn de Betfage li òke Olifi, nigbana ni Jesu rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji lọ. 2 O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá. 3 Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá. 4 Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe, 5 Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. 6 Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn. 7 Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a. 8 Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na. 9 Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun. 10 Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi? 11 Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.

Jesu Fòpin sí Ìwà Ìbàjẹ́ ninu Tẹmpili

12 Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. 13 O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà. 14 Ati awọn afọju ati awọn amukun wá sọdọ rẹ̀ ni tẹmpili; o si mu wọn larada. 15 Ṣugbọn nigbati awọn olori alufa ati awọn akọwe ri ohun iyanu ti o ṣe, ati bi awọn ọmọ kekeke ti nke ni tẹmpili, wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi; inu bi wọn gidigidi, 16 Nwọn si wi fun u pe, Iwọ gbọ́ eyiti awọn wọnyi nwi? Jesu si wi fun wọn pe, Bẹ̃ni; ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé? 17 O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀.

Jesu Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Gégùn-ún

18 Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a. 19 Nigbati o ri igi ọ̀pọtọ li ọ̀na, o lọ sibẹ̀, kò si ri ohun kan lori rẹ̀, bikoṣe kìki ewé, o si wi fun u pe, Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai. Lojukanna igi ọpọtọ na gbẹ. 20 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, ẹnu yà wọn, nwọn wipe, Igi ọpọtọ yi mà tete gbẹ? 21 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ. 22 Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ́, ẹnyin o ri gbà.

Ìjiyàn Lórí Agbára Jesu

23 Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi? 24 Jesu si dahun o si wi fun wọn pe, Emi ó si bi nyin lẽre ohun kan pẹlu, bi ẹnyin ba sọ fun mi, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi: 25 Baptismu Johanu, nibo li o ti wá? lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni, on o wi fun wa pe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́? 26 Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; awa mbẹ̀ru ijọ enia, nitori gbogbo wọn kà Johanu si wolĩ. 27 Nwọn si da Jesu lohùn, wipe, Awa ko mọ. O si wi fun wọn pe, Njẹ emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

Òwe nípa Àwọn Ọmọ Meji

28 Ṣugbọn kili ẹnyin nrò? ọkunrin kan wà ti o li ọmọ ọkunrin meji; o tọ̀ ekini wá, o si wipe, Ọmọ, lọ iṣiṣẹ loni ninu ọgba ajara mi. 29 O si dahùn wipe, Emi kì yio lọ: ṣugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ. 30 O si tọ̀ ekeji wá, o si wi bẹ̃ gẹgẹ. O si dahùn wi fun u pe, Emi o lọ, baba: kò si lọ. 31 Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun. 32 Nitori Johanu ba ọ̀na ododo tọ̀ nyin wá, ẹnyin kò si gbà a gbọ́: ṣugbọn awọn agbowode ati awọn panṣaga gbà a gbọ́: ṣugbọn ẹnyin, nigbati ẹnyin si ri i, ẹ kò ronupiwada nikẹhin, ki ẹ le gbà a gbọ́.

Òwe nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà

33 Ẹ gbọ́ owe miran; Bãle ile kan wà ti o gbìn ajara, o si sọgba yi i ká, o wà ibi ifunti sinu rẹ̀, o kọ́ ile-iṣọ, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si ajò. 34 Nigbati akokò eso sunmọ etile, o ràn awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si awọn oluṣọgba na, ki nwọn ki o le gbà wá ninu eso rẹ̀. 35 Awọn oluṣọgba si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn lù ekini, nwọn pa ekeji, nwọn si sọ ẹkẹta li okuta. 36 O si tun rán awọn ọmọ-ọdọ miran ti o jù awọn ti iṣaju lọ: nwọn si ṣe bẹ̃ si wọn gẹgẹ. 37 Ṣugbọn ni ikẹhin gbogbo wọn, o rán ọmọ rẹ̀ si wọn, o wipe, Nwọn o ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. 38 Ṣugbọn nigbati awọn oluṣọgba ri ọmọ na, nwọn wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rẹ̀. 39 Nwọn si mu u, nwọn wọ́ ọ jade kuro ninu ọgbà ajara na, nwọn si pa a. 40 Njẹ nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni? 41 Nwọn wi fun u pe, Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran, awọn ti o ma fi eso rẹ̀ fun u lakokò. 42 Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a ninu iwe mimọ́ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? 43 Nitorina emi wi fun nyin pe, A o gbà ijọba Ọlọrun lọwọ nyin, a o si fifun orilẹ-ede ti yio ma mu eso rẹ̀ wá. 44 Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta yi yio fọ́: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lũlu. 45 Nigbati awọn olori alufa ati awọn Farisi gbọ́ owe rẹ̀ nwọn woye pe awọn li o mba wi. 46 Ṣugbọn nigbati nwọn nwá ọ̀na ati gbé ọwọ́ le e, nwọn bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.

Matteu 22

Òwe Àsè Igbeyawo

1 Jesu si dahùn, o si tún fi owe sọ̀rọ fun wọn pe, 2 Ijọba ọrun dabi ọba kan, ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rẹ̀. 3 O si rán awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọ ipè awọn ti a ti pè tẹlẹ si ibi iyawo: ṣugbọn nwọn kò fẹ wá. 4 O si tún rán awọn ọmọ-ọdọ miran, wipe, Ẹ wi fun awọn ti a pè pe, Wò o, mo se onjẹ mi tan: a pa malu ati gbogbo ẹran abọpa mi, a si ṣe ohun gbogbo tan: ẹ wá si ibi iyawo. 5 Ṣugbọn nwọn ko fi pè nkan, nwọn ba tiwọn lọ, ọkan si ọ̀na oko rẹ̀, omiran si ọ̀na òwò rẹ̀: 6 Awọn iyokù si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn ṣe àbuku si wọn, nwọn si lù wọn pa. 7 Nigbati ọba si gbọ́ eyi, o binu: o si rán awọn ogun rẹ̀ lọ, o pa awọn apania wọnni run, o si kun ilu wọn. 8 Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A se ase iyawo tan, ṣugbọn awọn ti a ti pè kò yẹ. 9 Nitorina ẹ lọ si ọ̀na opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo. 10 Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun. 11 Nigbati ọba na wá iwò awọn ti o wá jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ̀ ti kò wọ̀ aṣọ iyawo: 12 O si bi i pe, Ọrẹ́, iwọ ti ṣe wọ̀ ìhin wá laini aṣọ iyawo? Kò si le fọhùn. 13 Nigbana li ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà. 14 Nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.

Ọ̀rọ̀ Jesu nípa Sísan Owó-orí fún Kesari

15 Nigbana li awọn Farisi lọ, nwọn gbìmọ bi nwọn o ti ṣe ri ọ̀rọ gbámọ ọ li ẹnu. 16 Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia. 17 Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? o tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́? 18 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe? 19 Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá. 20 O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? 21 Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. 22 Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ.

Ìjiyàn lórí Ajinde Àwọn Òkú

23 Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i, 24 Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀. 25 Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀: 26 Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje. 27 Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. 28 Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i. 29 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun. 30 Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun. 31 Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe, 32 Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye. 33 Nigbati awọn enia gbọ́ eyi, ẹnu yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀.

Òfin tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ

34 Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́ pe, o pa awọn Sadusi li ẹnu mọ́, nwọn pè ara wọn jọ. 35 Nigbana li ọkan ninu wọn, ti iṣe amofin, ndán a wò, o si bi i lẽre ọ̀rọ kan, wipe, 36 Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin? 37 Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. 38 Eyi li ekini ati ofin nla. 39 Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. 40 Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́.

Ọ̀rọ̀ Iyàn lórí Ẹni tí Í Ṣe Ọmọ Dafidi

41 Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn, 42 Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni. 43 O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe, 44 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? 45 Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀? 46 Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.

Matteu 23

Jesu Bá Àwọn Amòfin ati Àwọn Farisi Wí

1 NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, 2 Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose: 3 Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe. 4 Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na. 5 Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn. 6 Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu, 7 Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi. 8 Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin. 9 Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun. 10 Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi. 11 Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin. 12 Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga.

Jesu Dá Àwọn Amòfin ati Àwọn Farisi Lẹ́bi

13 Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle. 14 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin jẹ ile awọn opó run, ati nitori aṣehan, ẹ ngbadura gigun: nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọ̀ju. 15 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ. 16 Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese. 17 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́? 18 Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese. 19 Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́? 20 Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀. 21 Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀. 22 Ẹniti o ba si fi ọrun bura, o fi itẹ́ Ọlọrun bura, ati ẹniti o joko lori rẹ̀. 23 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe. 24 Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì. 25 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia. 26 Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu. 27 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo. 28 Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu ẹ kún fun agabagebe ati ẹ̀ṣẹ.

Wọn Yóo Jèrè Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn

29 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin kọ́ ibojì awọn wolĩ, ẹnyin si ṣe isà okú awọn olododo li ọṣọ, 30 Ẹnyin si wipe, Awa iba wà li ọjọ awọn baba wa, awa kì ba li ọwọ́ ninu ẹ̀jẹ awọn wolĩ. 31 Njẹ ẹnyin li ẹlẹri fun ara nyin pe, ẹnyin li awọn ọmọ awọn ẹniti o pa awọn wolĩ. 32 Njẹ ẹnyin kuku kún òṣuwọn baba nyin de oke. 33 Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi? 34 Nitorina ẹ kiyesi i, Emi rán awọn wolĩ, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin ó si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu: 35 Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ. 36 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo nkan wọnyi ni yio wá sori iran yi.

Jesu Kẹ́dùn fún Jerusalẹmu

37 Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! 38 Sawò o, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro. 39 Mo si wi fun nyin, Ẹnyin kì yio ri mi mọ́ lati isisiyi lọ, titi ẹnyin o fi wipe, Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.

Matteu 24

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Wíwó Tẹmpili

1 JESU si jade lọ, o ti tẹmpili kuro: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá lati fi kikọ́ tẹmpili hàn a. 2 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ri gbogbo nkan wọnyi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Kì yio si okuta kan nihinyi ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrora

3 Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá nikọ̀kọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye? 4 Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ. 5 Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. 6 Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. 7 Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: ìyan, ati ajakalẹ-arùn, ati iṣẹlẹ̀ yio si wà ni ibi pipọ. 8 Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. 9 Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi. 10 Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn. 11 Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. 12 Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù. 13 Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà. 14 A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.

Àkókò Iṣẹ́ Ńlá

15 Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:) 16 Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke: 17 Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: 18 Ki ẹniti mbẹ li oko maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. 19 Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! 20 Ẹ si mã gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutù, tabi ọjọ isimi: 21 Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si. 22 Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru. 23 Nigbana bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, Wo o, Kristi mbẹ nihin, tabi lọhun; ẹ máṣe gbà a gbọ́. 24 Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolĩ yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu nla hàn; tobẹ̃ bi o le ṣe ṣe nwọn o tàn awọn ayanfẹ pãpã. 25 Wo o, mo wi fun nyin tẹlẹ. 26 Nitorina bi nwọn ba wi fun nyin pe, Wo o, o wà li aginjù; ẹ má lọ sibẹ̀: wo o, o wà ni iyẹwu; ẹ máṣe gbàgbọ́. 27 Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de ìwọ-õrun; bẹ̃ni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. 28 Nitori ibikibi ti oku ba gbé wà, ibẹ̀ li awọn igúnnugún ikojọ pọ̀ si.

Dídé ti Ọmọ-Eniyan

29 Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mì titi: 30 Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla. 31 Yio si rán awọn angẹli rẹ̀ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji.

Ẹ̀kọ́ Ara Igi Ọ̀pọ̀tọ́

32 Njẹ ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: 33 Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. 34 Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. 35 Ọrun on aiye yio rekọjá, ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Kò Sí Ẹni tí Ó Mọ Ọjọ́ náà Gan-an

36 Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. 37 Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio si ri. 38 Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, 39 Nwọn kò si mọ̀ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. 40 Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ. 41 Awọn obinrin meji yio jùmọ ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. 42 Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ̀ wakati ti Oluwa nyin yio de. 43 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna, on kì ba ti jẹ́ ki a runlẹ ile rẹ̀. 44 Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de.

Oríṣìí Ẹrú Meji

45 Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò? 46 Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ẹniti yio bá a ki o mã ṣe bẹ̃. 47 Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni. 48 Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi fà àbọ rẹ̀ sẹhin; 49 Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti; 50 Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba. 51 Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rẹ̀ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Matteu 25

Òwe nípa Àwọn Wundia Mẹ́wàá

1 NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo. 2 Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn. 3 Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ: 4 Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu oróro ninu kolobo pẹlu fitila wọn. 5 Nigbati ọkọ iyawo pẹ, gbogbo wọn tõgbé, nwọn si sùn. 6 Ṣugbọn lãrin ọganjọ, igbe ta soke, wipe, Wo o, ọkọ, iyawo mbọ̀; ẹ jade lọ ipade rẹ̀. 7 Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe. 8 Awọn alaigbọn si wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu oróro nyin; nitori fitila wa nkú lọ. 9 Ṣugbọn awọn ọlọ́gbọn da wọn li ohùn, wipe, Bẹ̃kọ; ki o má ba ṣe alaito fun awa ati ẹnyin: ẹ kuku tọ̀ awọn ti ntà lọ, ki ẹ si rà fun ara nyin. 10 Nigbati nwọn si nlọ rà, ọkọ iyawo de; awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ si ibi iyawo: a si tì ilẹkun. 11 Ni ikẹhin li awọn wundia iyokù si de, nwọn nwipe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa. 12 Ṣugbọn o dahùn, wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin. 13 Nitorina, ẹ ma ṣọna, bi ẹnyin ko ti mọ̀ ọjọ, tabi wakati ti Ọmọ-enia yio de.

Òwe nípa Àwọn Ẹrú Mẹta

14 Nitori ijọba ọrun dabi ọkunrin kan ti o nlọ si àjo, ẹniti o pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si kó ẹrù rẹ̀ fun wọn. 15 O si fi talenti marun fun ọkan, o fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fifun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkanna o mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n. 16 Nigbana li eyi ti o gbà talenti marun lọ, ọ fi tirẹ̀ ṣòwo, o si jère talenti marun miran. 17 Gẹgẹ bẹ̃li eyi ti o gbà meji, on pẹlu si jère meji miran. 18 Ṣugbọn eyi ti o gbà talenti kan lọ, o wà ilẹ, o si rì owo oluwa rẹ̀. 19 Lẹhin igba ti o pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni de, o ba wọn ṣiro. 20 Eyi ti o gbà talenti marun si wá, o si mu talenti marun miran wá pẹlu, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti marun fun mi: si wò o, mo jère talenti marun miran. 21 Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ. 22 Eyi ti o gbà talenti meji pẹlu si wá, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wo o, mo jère talenti meji miran. 23 Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ. 24 Eyi ti o gbà talenti kan si wá, o ni, Oluwa, mo mọ̀ ọ pe onroro enia ni iwọ iṣe, iwọ nkore nibiti iwọ kò gbe funrugbin si, iwọ si nṣà nibiti iwọ kò fẹ́ka si: 25 Emi si bẹ̀ru, mo si lọ pa talenti rẹ mọ́ ninu ilẹ: wo o, nkan rẹ niyi. 26 Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si: 27 Nitorina iwọ iba fi owo mi si ọwọ́ awọn ti npowodà, nigbati emi ba de, emi iba si gbà nkan mi pẹlu elé. 28 Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa. 29 Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni. 30 Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-èdè

31 Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀: 32 Niwaju rẹ̀ li a o si kó gbogbo orilẹ ède jọ: yio si yà wọn si ọ̀tọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ: 33 On o si fi agutan si ọwọ́ ọtún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsi. 34 Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa: 35 Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile: 36 Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá. 37 Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu? 38 Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ? 39 Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá? 40 Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi. 41 Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ́ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀: 42 Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu: 43 Mo jẹ alejò, ẹnyin kò gbà mi si ile: mo wà ni ìhoho, ẹnyin kò si daṣọ bò mi: mo ṣàisan, mo si wà ninu tubu, ẹnyin kò bojuto mi. 44 Nigbana ni awọn pẹlu yio dahùn wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, tabi ti iwọ jẹ alejò, tabi ti iwọ wà ni ìhoho, tabi ninu aisan, tabi ninu tubu, ti awa kò si ṣe iranṣẹ fun ọ? 45 Nigbana ni yio da wọn lohun wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi. 46 Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu ìya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si ìye ainipẹkun.

Matteu 26

Àwọn Juu dìtẹ̀ láti pa Jesu

1 O SI ṣe, nigbati Jesu pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, 2 Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu. 3 Nigbana li awọn olori alufa, awọn akọwe, ati awọn àgba awọn enia pejọ li ãfin olori alufa, ẹniti a npè ni Kaíafa, 4 Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a. 5 Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia.

Obinrin kan Fi Òróró Kun Jesu ní Bẹtani

6 Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, 7 Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ. 8 Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo? 9 A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà. 10 Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara. 11 Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn ẹnyin kò ni mi nigbagbogbo. 12 Nitori li eyi ti obinrin yi dà ororo ikunra yi si mi lara, o ṣe e fun sisinku mi. 13 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a ba gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ pẹlu li a o si ròhin eyi ti obinrin yi ṣe, ni iranti rẹ̀.

Judasi Gbà láti Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

14 Nigbana li ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Judasi Iskariotu tọ̀ awọn olori alufa lọ, 15 O si wipe, Kili ẹnyin o fifun mi, emi o si fi i le nyin lọwọ? Nwọn si ba a ṣe adehùn ọgbọ̀n owo fadaka. 16 Lati igba na lọ li o si ti nwá ọ̀na lati fi i le wọn lọwọ.

Jesu Jẹ Àsè Ìrékọjá pẹlu Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn

17 Nigba ọjọ ikini ajọ aiwukara, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse silẹ dè ọ lati jẹ irekọja? 18 O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi. 19 Awọn ọmọ-ẹhin na si ṣe gẹgẹ bi Jesu ti fi aṣẹ fun wọn; nwọn si pèse irekọja silẹ. 20 Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila. 21 Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. 22 Nwọn si kãnu gidigidi, olukuluku wọn bẹ̀rẹ si ibi i lẽre pe, Oluwa, emi ni bi? 23 O si dahùn wipe, Ẹniti o bá mi tọwọ bọ inu awo, on na ni yio fi mi hàn. 24 Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lati ọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a ko bí i. 25 Nigbana ni Judasi, ti o fi i hàn, dahùn wipe, Rabbi, emi ni bi? O si wi fun u pe, Iwọ wi i.

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

26 Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Gbà, jẹ; eyiyi li ara mi. 27 O si mu ago, o dupẹ, o si fifun wọn, o wipe, Gbogbo nyin ẹ mu ninu rẹ̀; 28 Nitori eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia fun imukuro ẹ̀ṣẹ. 29 Ṣugbọn mo wi fun nyin, lati isisiyi lọ emi kì yio mu ninu eso ajara yi mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o si bá nyin mu titun ni ijọba Baba mi. 30 Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi. 31 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru yi: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o kọlù oluṣọ-agutan, a o si tú agbo agutan na ká kiri. 32 Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili. 33 Peteru si dahùn o wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀ lara rẹ, emi kì yio kọsẹ̀ lai. 34 Jesu wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, Li oru yi ki akukọ ki o to kọ iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta. 35 Peteru wi fun u pe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi kò jẹ sẹ́ ọ. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin wi pẹlu.

Adura Jesu ní Gẹtisemani

36 Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi. 37 O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì. 38 Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na. 39 O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ. 40 O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan? 41 Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara. 42 O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu u, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe. 43 O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun. 44 O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna. 45 Nigbana li o tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: wo o, wakati kù fẹfẹ, ti a o si fi Ọmọ-ẹnia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ. 46 Ẹ dide, ki a mã lọ: wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.

Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

47 Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá. 48 Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu ko li ẹnu, on na ni: ẹ mú u. 49 Lojukanna o wá sọdọ Jesu, o si wipe, Alafia, Olukọni; o si fi ẹnu ko o li ẹnu. 50 Jesu si wi fun u pe, Ọrẹ́, nitori kini iwọ fi wá? Nigbana ni nwọn wá, nwọn si gbé ọwọ́ le Jesu, nwọn si mu u. 51 Si wo o, ọkan ninu awọn ti o wà pẹlu Jesu nà ọwọ́ rẹ̀, o si fà idà rẹ̀ yọ, o si ṣá ọkan ti iṣe ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke e li etí sọnù. 52 Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Fi idà rẹ si ipò rẹ̀: nitoripe gbogbo awọn ti o mu idà ni yio ti ipa idà ṣegbé. 53 Iwọ ṣebi emi ko le kepè Baba mi, on iba si fun mi jù legioni angẹli mejila lọ lojukanna yi? 54 Ṣugbọn iwe-mimọ́ yio ha ti ṣe ti yio fi ṣẹ, pe bẹ̃ni yio ri? 55 Ni wakati na ni Jesu wi fun ijọ enia pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? li ojojumọ li emi mba nyin joko ni tẹmpili ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si gbé ọwọ́ le mi. 56 Ṣugbọn gbogbo eyi ṣe, ki iwe-mimọ́ awọn wolĩ ba le ṣẹ. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi i silẹ, nwọn si sá lọ.

A Mú Jesu Lọ siwaju Ìgbìmọ̀

57 Awọn ti o si mu Jesu, fà a lọ si ile Kaiafa, olori alufa, nibiti awọn akọwe ati awọn agbàgba gbé pejọ si. 58 Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere titi fi de agbala olori alufa, o bọ́ si ile, o si bá awọn ọmọ-ọdọ na joko lati ri opin rẹ̀. 59 Nigbana li olori alufa, ati awọn alàgba, ati gbogbo ajọ igbimọ nwá ẹlẹri eke si Jesu lati pa a; 60 Ṣugbọn nwọn ko ri ohun kan: otitọ li ọ̀pọ ẹlẹri eke wá, ṣugbọn nwọn kò ri ohun kan. Nikẹhin li awọn ẹlẹri eke meji wá; 61 Nwọn wipe, ọkunrin yi wipe, Emi le wó tẹmpili Ọlọrun, emi o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta. 62 Olori alufa si dide, o si wi fun u pe, Iwọ ko dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? 63 Ṣugbọn Jesu dakẹ. Olori alufa dahùn o si wi fun u pe, Mo fi Ọlọrun alãye bẹ̀ ọ pé, ki iwọ ki o sọ fun wa bi iwọ ba ṣe Kristi Ọmọ Ọlọrun. 64 Jesu wi fun u pe, Iwọ wi i: ṣugbọn mo wi fun nyin, Lẹhin eyi li ẹnyin o ri Ọmọ-enia ti yio joko li ọwọ́ ọtún agbara, ti yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. 65 Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, O sọ ọrọ-odi; ẹlẹri kili a si nwá? wo o, ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na nisisiyi. 66 Ẹnyin ti rò o si? Nwọn dahùn, wipe, O jẹbi ikú. 67 Nigbana ni nwọn tutọ́ si i loju, nwọn kàn a lẹṣẹ́; awọn ẹlomiran fi atẹ́lọwọ́ wọn gbá a loju; 68 Nwọn wipe, Sọtẹlẹ fun wa, iwọ, Kristi, tali ẹniti o nlù ọ ni?

Peteru Sẹ́ Jesu

69 Peteru joko lode li ãfin: nigbana ni ọmọbinrin kan tọ̀ ọ wá, o wipe, Iwọ pẹlu wà pẹlu Jesu ti Galili. 70 Ṣugbọn o sẹ́ li oju gbogbo wọn, o wipe, Emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. 71 Nigbati o si jade si iloro, ọmọbinrin miran si ri i, o si wi fun awọn ti o wà nibẹ̀ pe, ọkunrin yi wà pẹlu Jesu ti Nasareti. 72 O si tun fi èpe sẹ́, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na. 73 Nigbati o pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun Peteru pe, Lõtọ ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe; nitoripe ohùn rẹ fi ọ hàn. 74 Nigbana li o bẹ̀rẹ si ibura ati si iré, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na. Lojukanna akukọ si kọ. 75 Peteru si ranti ọ̀rọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi lẹrinmẹta. O si bọ si ode, o sọkun kikorò.

Matteu 27

Wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu

1 NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a: 2 Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ.

Ikú Judasi

3 Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba. 4 O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o. 5 O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso. 6 Awọn olori alufa si mu owo fadaka na, nwọn si wipe, Ko tọ́ ki a fi i sinu iṣura, nitoripe owo ẹ̀jẹ ni. 7 Nwọn si gbìmọ, nwọn si fi rà ilẹ amọ̀koko, lati ma sinkú awọn alejò ninu rẹ̀. 8 Nitorina li a ṣe npè ilẹ na ni Ilẹ ẹ̀jẹ, titi di ọjọ oni. 9 Nigbana li eyi ti Jeremiah wolĩ sọ wá ṣẹ, pe, Nwọn si mu ọgbọ̀n owo fadaka na, iye owo ẹniti a diyele, ẹniti awọn ọmọ Israeli diyele; 10 Nwọn si fi rà ilẹ, amọ̀koko, gẹgẹ bi Oluwa ti làna silẹ fun mi.

Pilatu Fi Ọ̀rọ̀ Wá Jesu Lẹ́nu Wò

11 Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i. 12 Nigbati a si nkà si i lọrùn lati ọwọ́ awọn olori alufa, ati awọn àgbãgba wá, on kò dahùn kan. 13 Nigbana ni Pilatu wi fun u pe, Iwọ ko gbọ́ ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ? 14 On kò si dá a ni gbolohun kan; tobẹ̃ ti ẹnu yà Bãlẹ gidigidi.

A Dá Jesu Lẹ́bi Ikú

15 Nigba ajọ na, Bãlẹ a mã dá ondè kan silẹ fun awọn enia, ẹnikẹni ti nwọn ba fẹ. 16 Nwọn si ni ondè buburu kan lakoko na, ti a npè ni Barabba. 17 Nitorina nigbati nwọn pejọ, Pilatu wi fun wọn pe, Tali ẹnyin nfẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Barabba, tabi Jesu ti a npè ni Kristi? 18 O sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni nwọn ṣe fi i le on lọwọ. 19 Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀. 20 Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn agbàgba yi ijọ enia li ọkàn pada lati bère Barabba, ki nwọn si pa Jesu. 21 Bãlẹ dahùn o si wi fun wọn pe, Ninu awọn mejeji, ewo li ẹnyin fẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Nwọn wipe, Barabba. 22 Pilatu bi wọn pe, Kili emi o ha ṣe si Jesu ẹniti a npè ni Kristi? Gbogbo wọn wipe, Ki a kàn a mọ agbelebu. 23 Bãlẹ si bère wipe, Ẽṣe, buburu kili o ṣe? Ṣugbọn nwọn kigbe soke si i pe, Ki a kàn a mọ agbelebu. 24 Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o. 25 Nigbana ni gbogbo enia dahùn, nwọn si wipe, Ki ẹjẹ rẹ̀ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa. 26 Nigbana li o da Barabba silẹ fun wọn. Ṣugbọn o nà Jesu, o si fi i le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.

Àwọn Ọmọ-ogun fi Jesu Ṣẹ̀sín

27 Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. 28 Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. 29 Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. 30 Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. 31 Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu.

A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

32 Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀. 33 Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Golgota, eyini ni, Ibi agbari, 34 Nwọn fi ọti kikan ti a dàpọ mọ orõrò fun u lati mu: nigbati o si tọ́ ọ wò, o kọ̀ lati mu u. 35 Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu, nwọn pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gègé le e: ki eyi ti wolĩ wi ba le ṣẹ, pe, Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn aṣọ ileke mi ni nwọn ṣẹ gègé le. 36 Nwọn si joko, nwọn nṣọ ọ nibẹ̀. 37 Nwọn si fi ọ̀ran ifisùn rẹ̀ ti a kọ si igberi rẹ̀, EYI NI JESU ỌBA AWỌN JU. 38 Nigbana li a kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi. 39 Awọn ti nkọja lọ si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, 40 Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá. 41 Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, 42 O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. 43 O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi. 44 Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna.

Ikú Jesu

45 Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. 46 Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? 47 Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọkunrin yi npè Elijah. 48 Lojukanna ọkan ninu wọn si sare, o mu kànìnkànìn, o tẹ̀ ẹ bọ̀ inu ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o si fifun u mu. 49 Awọn iyokù wipe, Ẹ fi silẹ̀, ẹ jẹ ki a mã wò bi Elijah yio wá gbà a là. 50 Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. 51 Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; 52 Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, 53 Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia. 54 Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe. 55 Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u: 56 Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede.

Ìsìnkú Jesu

57 Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu: 58 O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u. 59 Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i, 60 O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ. 61 Maria Magdalene si wà nibẹ̀, ati Maria keji, nwọn joko dojukọ ibojì na.

A Fi Àwọn Ọmọ-ogun Ṣọ́ Ibojì Jesu

62 Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu, 63 Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde. 64 Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju. 65 Pilatu wi fun wọn pe, Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mã lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e. 66 Bẹ̃ni nwọn lọ, nwọn si se iboji na daju, nwọn fi edídí dí okuta na, nwọn si yàn iṣọ.

Matteu 28

Ajinde Jesu

1 LI opin ọjọ isimi, bi ilẹ ọjọ kini ọ̀sẹ ti bèrẹ si imọ́, Maria Magdalene ati Maria keji wá lati wò ibojì na. 2 Si wò o, ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko le e. 3 Oju rẹ̀ dabi manamana, aṣọ rẹ̀ si fún bi ẹ̀gbọn owu: 4 Nitori ẹ̀ru rẹ̀ awọn oluṣọ warìri, nwọn si dabi okú. 5 Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu. 6 Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si. 7 Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin. 8 Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 9 Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u. 10 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi.

Ìròyìn Àwọn tí Ń Ṣọ́ Ibojì

11 Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa. 12 Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na, 13 Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn. 14 Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ. 15 Bẹ̃ni nwọn gbà owo na, nwọn si ṣe gẹgẹ bi a ti kọ́ wọn: ọ̀rọ yi si di rirò kiri lọdọ awọn Ju titi di oni.

Jesu Rán Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ Níṣẹ́

16 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn. 17 Nigbati nwọn si ri i, nwọn foribalẹ fun u: ṣugbọn awọn miran ṣiyemeji. 18 Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi. 19 Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́: 20 Ki ẹ ma kọ́ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin.

Marku 1

Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi

1 IBẸRẸ ihinrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. 2 Bi a ti kọ ọ ninu iwe woli Isaiah: Kiyesi i, mo rán onṣẹ mi ṣiwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. 3 Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju ọ̀na rẹ̀ tọ́. 4 Johanu de, ẹniti o mbaptisi ni iju, ti o si nwasu baptismu ironupiwada fun idariji ẹ̀ṣẹ. 5 Gbogbo ilẹ Judea, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu jade tọ̀ ọ lọ, a si ti ọwọ́ rẹ̀ baptisi gbogbo wọn li odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. 6 Johanu si wọ̀ aṣọ irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀; o si njẹ ẽṣú ati oyin ìgan. 7 O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú: 8 Emi fi omi baptisi nyin; ṣugbọn on yio fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.

Jesu Ṣe Ìrìbọmi

9 O si ṣe li ọjọ wọnni, Jesu jade wá lati Nasareti ti Galili, a si ti ọwọ́ Johanu baptisi rẹ̀ li odò Jordani. 10 Lojukanna bi o si ti goke lati inu omi wá, o ri ọrun pinya, Ẹmi nsọkalẹ bi àdaba le e lori: 11 Ohùn kan si ti ọrun wá, wipe, Iwọ ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Satani Dán Jesu Wò

12 Loju kan náà Ẹmí si dari rẹ̀ si ijù. 13 O si wà ni ogoji ọjọ ni ijù, a ti ọwọ́ Satani dán an wò, o si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ́; awọn angẹli si nṣe iranṣẹ fun u.

Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Galili

14 Lẹhin igbati a fi Johanu sinu tubu tan, Jesu lọ si Galili, o nwasu ihinrere ijọba Ọlọrun, 15 O si nwipe, Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gbà ihinrere gbọ́.

Jesu Pe Apẹja Mẹrin

16 Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja. 17 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi o si sọ nyin di apẹja enia. 18 Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. 19 Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn. 20 Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

Ọkunrin Ẹlẹ́mìí Èṣù

21 Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni. 22 Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe. 23 Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke. 24 O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun. 25 Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀. 26 Nigbati ẹmi aimọ́ na si gbé e ṣanlẹ, o ke li ohùn rara, o si jade kuro lara rẹ̀. 27 Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀. 28 Lojukanna okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo ẹkùn Galili ká.

Jesu Wo Ọpọlọpọ Eniyan Sàn

29 Nigbati nwọn si jade kuro ninu sinagogu, lojukanna nwọn wọ̀ ile Simoni ati Anderu, pẹlu Jakọbu ati Johanu. 30 Iya aya Simoni si dubulẹ aìsan ibà, nwọn si sọ ọ̀ran rẹ̀ fun u. 31 O si wá, o fà a lọwọ, o si gbé e dide; lojukanna ibà na si fi i silẹ, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. 32 Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá. 33 Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na. 34 O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ.

Jesu Waasu ní Galili

35 O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura. 36 Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a. 37 Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ. 38 O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá. 39 O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade.

Jesu Wo Alárùn Ẹ̀tẹ̀ Sàn

40 Ọkunrin kan ti o dẹtẹ si tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ niwaju rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. 41 Jesu ṣãnu rẹ̀, o nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o si wi fun u pe, Mo fẹ, iwọ di mimọ́. 42 Bi o si ti sọ̀rọ, lojukanna ẹ̀tẹ na fi i silẹ; o si di mimọ́. 43 O si kìlọ fun u gidigidi, lojukanna o si rán a lọ; 44 O si wi fun u pe, Wo o, máṣe sọ ohunkohun fun ẹnikẹni: ṣugbọn lọ, fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si fi ẹ̀bun iwẹnumọ́ rẹ ti Mose ti palaṣẹ, ni ẹrí fun wọn. 45 Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.

Marku 2

Jesu Wo Arọ Sàn

1 NIGBATI o si tún wọ̀ Kapernaumu lọ lẹhin ijọ melokan; okikí kàn yiká pe, o wà ninu ile. 2 Lojukanna ọ̀pọ enia si pejọ tobẹ̃ ti aye kò si fun wọn mọ, kò si, titi de ẹnu-ọ̀na: o si wasu ọ̀rọ na fun wọn. 3 Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé. 4 Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ. 5 Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. 6 Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe, 7 Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun? 8 Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin? 9 Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn? 10 Ṣugbọn ki ẹ le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) 11 Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ. 12 O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.

Jesu Pe Lefi

13 O si tún jade lọ si eti okun; gbogbo ijọ enia si wá sọdọ rẹ̀, o si kọ́ wọn. 14 Bi o si ti nkọja lọ, o ri Lefi ọmọ Alfeu, o joko ni bode, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin. 15 O si ṣe, bi o si ti joko tì onjẹ ni ile rẹ̀, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá bá Jesu joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nitoriti nwọn pọ̀ nwọn si tọ̀ ọ lẹhin. 16 Nigbati awọn akọwe ati awọn Farisi si ri i ti o mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽtiri ti o fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti o si mba wọn mu? 17 Nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kì iwá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn ko da: Emi ko wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Gbígbà

18 Awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi a ma gbàwẹ: nwọn si wá, nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi fi ngbàwẹ, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ? 19 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwe, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? niwọn igbati nwọn ni ọkọ iyawo lọdọ wọn, nwọn kò le gbàwẹ. 20 Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o gbàwẹ ni ijọ wọnni. 21 Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun mọ ogbologbo ẹ̀wu; bi bẹ̃ko eyi titun ti a fi lẹ ẹ a fà ogbologbo ya, aṣọ a si ma ya siwaju. 22 Ko si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bi bẹ̃kọ ọti-waini titun a bẹ́ ìgo na, ọti-waini a si danu, ìgo na a si fàya; ṣugbọn ọti-waini titun ni ã fi sinu ìgo titun.

Ìbéèrè Nípa Ọjọ́ Ìsinmi

23 O si ṣe, bi Jesu ti nkọja lọ lãrin oko ọkà li ọjọ isimi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà bi nwọn ti nlọ. 24 Awọn Farisi si wi fun u pe, Wo o, ẽṣe ti nwọn fi nṣe eyi ti kò yẹ li ọjọ isimi? 25 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati o ṣe alaini, ti ebi si npa a, on, ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀? 26 Bi o ti wọ̀ inu ile Ọlọrun lọ li ọjọ Abiatari olori alufa, ti o si jẹ akara ifihàn, ti ko tọ́ fun u lati jẹ bikoṣe fun awọn alufa, o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu? 27 O si wi fun wọn pe, A dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi: 28 Nitorina Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi pẹlu.

Marku 3

Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

1 O si tún wọ̀ inu sinagogu lọ; ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. 2 Nwọn si nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le fi i sùn. 3 O si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, duro larin. 4 O si wi fun wọn pe, O tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? nwọn si dakẹ. 5 Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji. 6 Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a.

Ọpọlọpọ Eniyan Lẹ́bàá Òkun

7 Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin, 8 Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá. 9 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u. 10 Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn. 11 Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun. 12 O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn. 13 O si gùn ori òke lọ, o si npè ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ̀: nwọn si tọ̀ ọ wá. 14 O si yàn awọn mejila, ki nwọn ki o le mã gbé ọdọ rẹ̀, ati ki o le ma rán wọn lọ lati wasu, 15 Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade: 16 Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru; 17 Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá: 18 Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote, 19 Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.

Jesu ati Beelisebulu

20 Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ. 21 Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ. 22 Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. 23 O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade? 24 Bi ijọba kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ijọba na kì yio le duro. 25 Bi ile kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ile na kì yio le duro. 26 Bi Satani ba si dide si ara rẹ̀, ti o si yàpa, on kì yio le duro, ṣugbọn yio ni opin. 27 Kò si ẹniti o le wọ̀ ile ọkunrin alagbara kan lọ, ki o si kó o li ẹrù lọ, bikoṣepe o tètekọ dè ọkunrin alagbara na li okùn; nigbana ni yio le kó o li ẹrù ni ile. 28 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo ẹ̀ṣẹ li a o dari wọn jì awọn ọmọ enia, ati gbogbo ọrọ-odi nipa eyiti nwọn o ma fi sọrọ-odi: 29 Ṣugbọn ẹniti o ba sọrọ-odi si Ẹmi Mimọ́ kì yio ni idariji titi lai, ṣugbọn o wà ninu ewu ẹbi ainipẹkun: 30 Nitoriti nwọn wipe, O li ẹmi aimọ́.

Àwọn Ta ni Ẹbí Jesu?

31 Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati iya rẹ̀ wá, nwọn duro lode, nwọn si ranṣẹ si i, nwọn npè e. 32 Awọn ọ̀pọ enia si joko lọdọ rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, Wò o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ nwá ọ lode. 33 O si da wọn lohùn, wipe, Tani iṣe iya mi, tabi awọn arakunrin mi? 34 O si wò gbogbo awọn ti o joko lọdọ rẹ̀ yiká, o si wipe, Wò iya mi ati awọn arakunrin mi: 35 Nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe ifẹ Ọlọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.

Marku 4

Òwe Nípa Afunrugbin

1 O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun. 2 O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, 3 Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin; 4 O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. 5 Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ: 6 Ṣugbọn nigbati õrùn goke, o jóna; nitoriti kò ni gbongbo, o gbẹ. 7 Diẹ si bọ́ sarin ẹgún, nigbati ẹgún si dàgba soke, o fun u pa, kò si so eso. 8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, ti o ndagba ti o si npọ̀; o si mu eso jade wá, omiran ọgbọgbọn, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọ̀run. 9 O si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ, ki o gbọ́.

Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

10 Nigbati o kù on nikan, awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ pẹlu awọn mejila bi i lẽre idi owe na. 11 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn ti o wà lode, gbogbo ohun wọnyi li a nfi owe sọ fun wọn: 12 Nitori ni ríri ki nwọn ki o le ri, ki nwọn má si kiyesi; ati ni gbigbọ́ ki nwọn ki o le gbọ́, ki o má si yé wọn; ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba dari jì wọn.

Ìtumọ̀ Òwe Nípa Afunrugbin

13 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ owe yi? ẹnyin o ha ti ṣe le mọ̀ owe gbogbo? 14 Afunrugbin funrugbin ọ̀rọ na. 15 Awọn wọnyi si ni ti ẹba ọ̀na, nibiti a funrugbin ọ̀rọ na; nigbati nwọn si ti gbọ́, lojukanna Satani wá, o si mu ọ̀rọ na ti a fọn si àiya wọn kuro. 16 Awọn wọnyi pẹlu si li awọn ti a fun sori ilẹ apata; awọn ẹniti nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a fi ayọ̀ gbà a; 17 Nwọn kò si ni gbongbo ninu ara wọn, ṣugbọn nwọn a wà fun ìgba diẹ: lẹhinna nigbati wahalà tabi inunibini ba dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a kọsẹ̀. 18 Awọn wọnyi li awọn ti a fun sarin ẹgún; awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, 19 Aniyan aiye, ati itanjẹ ọrọ̀, ati ifẹkufẹ ohun miran si bọ sinu wọn, nwọn fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso. 20 Awọn wọnyi si li eyi ti a fún si ilẹ rere; irú awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti wọn si gbà a, ti wọn si so eso, omiran ọgbọgbọ̀n, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọrun.

Fìtílà Tí A Fi Òṣùwọ̀n Bò

21 O si wi fun wọn pe, A ha gbé fitilà wá lati fi sabẹ òṣuwọn, tabi sabẹ akete, ki a ma si ṣe gbé e kà ori ọpá fitilà? 22 Nitori kò si ohun ti o pamọ́ bikoṣe ki a le fi i hàn; bẹ̃ni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba. 23 Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. 24 O si wi fun wọn pe, Ẹ mã kiyesi ohun ti ẹnyin ngbọ́: òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o fi wọ̀n fun nyin: a o si fi kún u fun nyin. 25 Nitori ẹniti o ba ni, on li a o fifun: ati ẹniti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni.

Òwe Nípa Ìdàgbà Irúgbìn

26 O si wipe, Bẹ̃ sá ni ijọba Ọlọrun, o dabi ẹnipe ki ọkunrin kan funrugbin sori ilẹ; 27 Ki o si sùn, ki o si dide li oru ati li ọsán, ki irugbin na ki o si sọ jade ki o si dàgba, on kò si mọ̀ bi o ti ri. 28 Nitori ilẹ a ma so eso jade fun ara rẹ̀; ekini ẽhù, lẹhinna ipẹ́, lẹhinna ikunmọ ọkà ninu ipẹ́. 29 Ṣugbọn nigbati eso ba pọ́n tan, lojukanna on a tẹ̀ doje bọ inu rẹ̀ nitori igba ikorè de.

Òwe Nípa Wóró Mustardi

30 O si wipe, Kili a o fi ijọba Ọlọrun we? tabi kili a ba fi ṣe akawe rẹ̀? 31 O dabi wóro irugbin mustardi, eyiti, nigbati a gbin i si ilẹ, bi o tilẹ ṣe pe o kére jù gbogbo irugbin ti o wa ni ilẹ lọ, 32 Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀.

Jesu Ń Fi Òwe Pupọ Sọ̀rọ̀

33 Irù ọ̀pọ owe bẹ̃ li o fi mba wọn nsọ̀rọ, niwọn bi nwọn ti le gbà a si. 34 Ṣugbọn on kì iba wọn sọrọ laìsi owe: nigbati o ba si kù awọn nikan, on a si sọ idi ohun gbogbo fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Jesu Bá Ìgbì Omi Wí

35 Ni ijọ kanna, nigbati alẹ lẹ tan, o wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a rekọja lọ si apá keji. 36 Nigbati nwọn si ti tu ijọ ká, nwọn si gbà a gẹgẹ bi o ti wà sinu ọkọ̀. Awọn ọkọ̀ kekere miran pẹlu si wà lọdọ rẹ̀. 37 Ìji nla si dide, ìgbi si mbù sinu ọkọ̀, tobẹ̃ ti ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ si ikún. 38 On pãpã si wà ni idi ọkọ̀, o nsùn lori irọri: nwọn si jí i, nwọn si wi fun u pe, Olukọni, iwọ ko bikita bi awa ṣegbé? 39 O si ji, o ba afẹfẹ na wi, o si wi fun okun pe, Dakẹ jẹ. Afẹfẹ si da, iparọrọ nla si de. 40 O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ojo bẹ̃? ẹ kò ti iní igbagbọ sibẹ? 41 Ẹru si ba wọn gidigidi, nwọn si nwi fun ara wọn pe, Irú enia kili eyi, ti ati afẹfẹ ati okun gbọ́ tirẹ̀?

Marku 5

Jesu Mú Wèrè, Ará Geraseni, Lára dá

1 NWỌN si wá si apa keji okun ni ilẹ awọn ara Gadara. 2 Nigbati o si ti inu ọkọ̀ jade, lojukanna ọkunrin kan ti o li ẹmi aimọ pade rẹ̀, o nti ibi ibojì jade wá, 3 Ẹniti o ni ibugbe rẹ̀ ninu ibojì; kò si si ẹniti o le dè e, kò si, kì iṣe ẹ̀wọn: 4 Nitoripe nigbapupọ li a ti nfi ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹ̀wọn de e, on a si dá ẹ̀wọn na meji, a si dá ṣẹkẹṣẹkẹ wẹ́wẹ: bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o li agbara lati se e rọ̀. 5 Ati nigbagbogbo, li ọsán ati li oru, o wà lori òke, ati ninu ibojì, a ma kigbe, a si ma fi okuta pa ara rẹ̀ lara. 6 Ṣugbọn nigbati o ri Jesu li òkere, o sare wá, o si foribalẹ fun u, 7 O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró. 8 Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́. 9 O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀. 10 O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na. 11 Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ kan si wà nibẹ ti njẹ lẹba oke. 12 Gbogbo awọn ẹmi èṣu bẹ̀ ẹ wipe, Rán wa lọ sinu awọn ẹlẹdẹ, ki awa ki o le wọ̀ inu wọn lọ. 13 Lọgan Jesu si jọwọ wọn. Awọn ẹmi aimọ́ si jade, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tupũ nwọn si sure ni gẹrẹgẹrẹ lọ sinu okun (nwọn si to ìwọn ẹgbã;) nwọn si kú sinu okun. 14 Awọn ti mbọ́ wọn si sá, nwọn si lọ ròhin ni ilu nla, atì ni ilẹ na. Nwọn si jade lọ lati wò ohun na ti o ṣe. 15 Nwọn si wá sọdọ Jesu, nwọn si ri ẹniti o ti ni ẹmi èṣu, ti o si ni Legioni na, o joko, o si wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn. 16 Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ri fun ẹniti o li ẹmi èṣu, ati ti awọn ẹlẹdẹ pẹlu. 17 Nwọn si bẹ̀rẹ si ibẹ̀ ẹ, wipe, ki o lọ kuro li àgbegbe wọn. 18 Bi o si ti nwọ̀ inu ọkọ̀, ẹniti o ti li ẹmi èṣu na o mbẹ ẹ, ki on ki o le mã bá a gbé. 19 Ṣugbọn Jesu kò gbà fun u, ṣugbọn o wi fun u pe, Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ará ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣanu fun ọ. 20 O si pada lọ, o bẹ̀rẹ si ima ròhin ni Dekapoli, ohun nla ti Jesu ṣe fun u: ẹnu si yà gbogbo enia.

Ọmọdebinrin Jairu ati Obinrin kan Onísun Ẹ̀jẹ̀

21 Nigbati Jesu si tun ti inu ọkọ̀ kọja si apa keji, ọ̀pọ enia pejọ tì i: o si wà leti okun. 22 Si wo o, ọkan ninu awọn olori sinagogu, ti a npè ni Jairu, wa sọdọ rẹ̀; nigbati o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, 23 O si bẹ̀ ẹ gidigidi, wipe, Ọmọbinrin mi kekere wà loju ikú: mo bẹ̀ ọ ki o wá fi ọwọ́ rẹ le e, ki a le mu u larada: on o si yè. 24 O si ba a lọ; ọ̀pọ enia si ntọ̀ ọ lẹhin, nwọn si nhá a li àye. 25 Obinrin kan ti o ti ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, 26 Ẹniti oju rẹ̀ si ri ohun pipọ lọdọ ọ̀pọ awọn oniṣegun, ti o si ti ná ohun gbogbo ti o ni tan, ti kò si sàn rara, ṣugbọn kàka bẹ̃ o npọ̀ siwaju. 27 Nigbati o gburo Jesu, o wá sẹhin rẹ̀ larin ọ̀pọ enia, o fọwọ́kàn aṣọ rẹ̀. 28 Nitori o wipe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ mi kàn aṣọ rẹ̀, ara mi yio da. 29 Lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ; on si mọ̀ lara rẹ̀ pe, a mu on larada ninu arun na. 30 Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ? 31 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Iwọ ri bi ijọ enia ti nhá ọ li àye, iwọ si nwipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? 32 O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi. 33 Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u. 34 O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ. 35 Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu? 36 Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan. 37 Kò si jẹ ki ẹnikẹni tọ̀ on lẹhin, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin Jakọbu. 38 O si wá si ile olori sinagogu, o si ri ariwo, ati awọn ti nsọkun ti nwọn si npohunrere ẹkún gidigidi. 39 Nigbati o si wọle, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi npariwo, ti ẹ si nsọkun? ọmọ na ko kú, ṣugbọn sisùn li o sùn. 40 Nwọn si fi rẹrin ẹlẹya. Ṣugbọn nigbati o si tì gbogbo wọn jade, o mu baba ati iya ọmọ na, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, o si wọ̀ ibiti ọmọ na gbé dubulẹ si. 41 O si mu ọmọ na li ọwọ́, o wi fun u pe, Talita kumi; itumọ eyi ti ijẹ Ọmọbinrin, mo wi fun ọ, Dide. 42 Lọgan ọmọbinrin na si dide, o si nrìn; nitori ọmọ ọdún mejila ni. Ẹ̀ru si ba wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi. 43 O si paṣe fun wọn gidigidi pe, ki ẹnikẹni ki o máṣe mọ̀ eyi; o si wipe, ki nwọn ki o fun u li onjẹ.

Marku 6

A Kọ Jesu ní Nasarẹti

1 O SI jade nibẹ̀, o wá si ilu on tikararẹ̀; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. 2 Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? 3 Gbẹnagbẹna na kọ yi, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Jose, ati ti Juda, ati Simoni? awọn arabinrin rẹ̀ kò ha si wà nihinyi lọdọ wa? Nwọn si kọsẹ̀ lara rẹ̀. 4 Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀. 5 On ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ̀, jù pe o gbé ọwọ́ rẹ̀ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada. 6 Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni.

Jesu Rán Àwọn Mejila Níṣẹ́

7 O si pè awọn mejila na sọdọ rẹ̀, o bẹ̀rẹ si irán wọn lọ ni meji-meji; o si fi aṣẹ fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́; 8 O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe mu ohunkohun, lọ si àjo wọn, bikoṣe ọpá nikan; ki nwọn ki o máṣe mu àpo, tabi akara, tabi owo ninu asuwọn wọn: 9 Ṣugbọn ki nwọn ki o wọ̀ salubàta: ki nwọn máṣe wọ̀ ẹ̀wu meji. 10 O si wi fun wọn pe, Nibikibi ti ẹnyin ba wọ̀ ile kan, nibẹ̀ ni ki ẹ mã gbé titi ẹnyin o fi jade kuro nibẹ̀ na. 11 Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọrọ̀ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro nibẹ̀, ẹ gbọ̀n eruku ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu nla na lọ. 12 Nwọn si jade lọ, nwọn si wasu ki awọn enia ki o le ronupiwada. 13 Nwọn si lé ọ̀pọ awọn ẹmi èṣu jade, nwọn si fi oróro kùn ọ̀pọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, nwọn si mu wọn larada.

Ikú Johanu Onítẹ̀bọmi

14 Herodu ọba si gburo rẹ̀; (nitoriti okikí orukọ rẹ̀ kàn yiká:) o si wipe, Johanu Baptisti jinde kuro ninu oku, nitorina ni iṣẹ agbara ṣe nṣe lati ọwọ rẹ̀ wá. 15 Awọn ẹlomiran wipe, Elijah ni. Ṣugbọn awọn miran wipe, Woli kan ni, tabi bi ọkan ninu awọn woli. 16 Ṣugbọn nigbati Herodu gbọ́, o wipe, Johanu ni, ẹniti mo ti bẹ́ lori: on li o jinde kuro ninu okú. 17 Herodu tikararẹ̀ sá ti ranṣẹ mu Johanu, o si dè e sinu tubu nitori Herodia, aya Filippi arakunrin rẹ̀: on sá ti fi i ṣe aya. 18 Johanu sá ti wi fun Herodu pe, kò tọ́ fun iwọ lati ni aya arakunrin rẹ. 19 Nitorina ni Herodia ṣe ni i sinu, on si nfẹ ipa a; ṣugbọn kò le ṣe e: 20 Nitori Herodu bẹ̀ru Johanu, o si mọ̀ ọ li olõtọ enia ati ẹni mimọ́, o si ntọju rẹ̀; nigbati o gbọrọ rẹ̀, o ṣe ohun pipọ, o si fi ayọ̀ gbọrọ rẹ̀. 21 Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili; 22 Nigbati ọmọbinrin Herodia si wọle, ti o si njó, o mu inu Herodu dùn ati awọn ti o ba a joko, ọba si wi fun ọmọbinrin na pe, Bère ohunkohun ti iwọ fẹ lọwọ mi, emi o si fifun ọ. 23 O si bura fun u, wipe, Ohunkohun ti iwọ ba bere lọwọ mi, emi o si fifun ọ, titi fi de idameji ijọba mi. 24 O si jade lọ, o wi fun iya rẹ̀ pe, Kini ki emi ki o bère? On si wipe, Ori Johanu Baptisti. 25 Lojukanna, o si wọle tọ̀ ọba wá kánkan, o bère, wipe, emi nfẹ ki iwọ ki o fi ori Johanu Baptisti fun mi ninu awopọkọ nisisiyi. 26 Inu ọba si bajẹ gidigidi; ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati nitori awọn ti o bá a joko pọ̀, kò si fẹ ikọ̀ fun u. 27 Lọgan ọba si rán ẹṣọ́ kan, o fi aṣẹ fun u pe, ki o gbé ori rẹ̀ wá: o si lọ, o bẹ́ Johanu lori ninu tubu. 28 O si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, o si fi fun ọmọbinrin na: ọmọbinrin na si fi fun iya rẹ̀. 29 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́, nwọn wá, nwọn gbé okú rẹ̀, nwọn si lọ tẹ́ ẹ sinu ibojì.

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

30 Awọn aposteli si kó ara wọn jọ sọdọ Jesu, nwọn si ròhin ohungbogbo ti nwọn ti ṣe fun u, ati ohungbogbo ti nwọn ti kọni. 31 O si wi fun wọn pe, Ẹ wá ẹnyin tikaranyin si ibi ijù li apakan, ki ẹ si simi diẹ: nitori ọ̀pọlọpọ li awọn ti nwá ti nwọn si nlọ, nwọn kò tilẹ ri ãye tobẹ̃ ti nwọn iba fi jẹun. 32 Nwọn si ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù awọn nikan. 33 Awọn enia si ri wọn nigbati nwọn nlọ, ọ̀pọlọpọ si mọ̀ ọ, nwọn si sare ba ti ẹsẹ lọ sibẹ̀ lati ilu nla gbogbo wá, nwọn si ṣiwaju wọn, nwọn si jùmọ wá sọdọ rẹ̀. 34 Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ. 35 Nigbati ọjọ si bù lọ tan, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si bù lọ tan: 36 Rán wọn lọ, ki nwọn ki o le lọ si àgbegbe ilu, ati si iletò ti o yiká, ki nwọn ki o le rà onjẹ fun ara wọn: nitoriti nwọn kò li ohun ti nwọn o jẹ. 37 Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa o ha lọ irà akara igba owo idẹ ki a si fifun wọn jẹ? 38 O si wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? ẹ lọ wò o. Nigbati nwọn si mọ̀, nwọn wipe, Marun, pẹlu ẹja meji. 39 O si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o mu gbogbo wọn joko li ẹgbẹgbẹ lori koriko. 40 Nwọn si joko li ẹgbẹgbẹ li ọrọrun ati li aradọta. 41 Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn. 42 Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó. 43 Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu. 44 Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.

Jesu Rìn lórí Omi

45 Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká. 46 Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura. 47 Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ. 48 O si ri nwọn nṣiṣẹ ni wiwà ọkọ̀; nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn: nigbati o si di ìwọn iṣọ kẹrin oru, o tọ̀ wọn wá, o nrìn lori okun, on si nfẹ ré wọn kọja. 49 Ṣugbọn nigbati nwọn ri ti o nrìn loju omi, nwọn ṣebi iwin ni, nwọn si kigbe soke: 50 Nitori gbogbo wọn li o ri i, ti ẹ̀ru si ba wọn. Ṣugbọn lojukanna o si ba wọn sọ̀rọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ tújuka: Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. 51 O si wọ̀ inu ọkọ̀ tọ̀ wọn lọ; afẹfẹ si da: ẹ̀ru si ba wọn rekọja gidigidi ninu ara wọn, ẹnu si yà wọn. 52 Nwọn kò sá ronu iṣẹ iyanu ti iṣu akara: nitoriti ọkàn wọn le.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn ní Genesarẹti

53 Nigbati nwọn si rekọja tan, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti, nwọn si sunmọ eti ilẹ. 54 Bi nwọn si ti njade lati inu ọkọ̀ wá, lojukanna nwọn si mọ̀ ọ, 55 Nwọn si sare lọ si gbogbo igberiko yiká, nwọn bẹ̀rẹ si ima gbé awọn ti ara wọn ṣe alaida wá lori akete, si ibiti nwọn gbọ́ pe o wà. 56 Nibikibi ti o ba si gbé wọ̀, ni iletò gbogbo, tabi ilu nla, tabi arọko, nwọn ngbé olokunrun kalẹ ni igboro, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, a mu wọn larada.

Marku 7

Àṣà Ìbílẹ̀

1 AWỌN Farisi si pejọ sọdọ rẹ̀, ati awọn kan ninu awọn akọwe ti nwọn ti Jerusalemu wá. 2 Nigbati nwọn ri omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nfi ọwọ aimọ́ jẹun, eyini ni li aiwẹ̀ ọwọ́, nwọn mba wọn wijọ. 3 Nitori awọn Farisi, ati gbogbo awọn Ju, bi nwọn ko ba wẹ̀ ọwọ́ wọn gidigidi, nwọn ki ijẹun, nitoriti nwọn npa ofin atọwọdọwọ awọn àgba mọ́. 4 Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete. 5 Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun? 6 O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi. 7 Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, ti nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ́. 8 Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe. 9 O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́. 10 Mose sá wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ; ati Ẹnikẹni ti o ba sọrọ baba tabi iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀ na: 11 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bi enia ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi, Korbani ni, eyini ni Ẹbùn, o bọ́. 12 Bẹ̃li ẹnyin ko si jẹ ki o ṣe ohunkohun fun baba tabi iya rẹ̀ mọ́; 13 Ẹnyin nfi ofin atọwọdọwọ ti nyin, ti ẹ fi le ilẹ, sọ ọ̀rọ Ọlọrun di asan; ati ọpọ iru nkan bẹ̃ li ẹnyin nṣe.

Àṣà Ìbílẹ̀

14 Nigbati o si pè gbogbo awọn enia sọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ fi etí si mi olukuluku nyin, ẹ si kiyesi i: 15 Kò si ohunkokun lati ode enia, ti o wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ti o le sọ ọ di alaimọ́: ṣugbọn nkan wọnni ti o ti inu rẹ̀ jade, awọn wọnni ni isọ enia di alaimọ́. 16 Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. 17 Nigbati o si ti ọdọ awọn enia kuro wọ̀ inu ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre niti owe na. 18 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye tobẹ̃? ẹnyin ko kuku kiyesi pe, ohunkohun ti o wọ̀ inu enia lati ode lọ, ko le sọni di alaimọ́; 19 Nitoriti ko lọ sinu ọkàn rẹ̀, ṣugbọn sinu ara, a si yà a jade, a si gbá gbogbo onjẹ danù? 20 O si wipe, Eyi ti o ti inu enia jade, eyini ni isọ enia di alaimọ́. 21 Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania, 22 Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère: 23 Lati inu wá ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ́.

Igbagbọ Obinrin Ará Fonikia

24 O si dide ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni, o si wọ̀ inu ile kan, ko si fẹ ki ẹnikẹni ki o mọ̀: ṣugbọn on kò le fi ara pamọ́. 25 Nitori obinrin kan, ẹniti ọmọbinrin rẹ̀ kekere li ẹmi aimọ́ gburo rẹ̀, o wá, o si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀: 26 Hellene si li obinrin na, Sirofenikia ni orilẹ-ède rẹ̀; o si bẹ̀ ẹ ki on iba lé ẹmi èṣu na jade lara ọmọbinrin rẹ̀. 27 Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Jẹ ki a kọ́ fi onjẹ tẹ awọn ọmọ lọrun na: nitoriti ko tọ́ lati mu onjẹ awọn ọmọ, ki a si fi i fun ajá. 28 O si dahùn o si wi fun u pe, Bẹni Oluwa: ṣugbọn awọn ajá pãpã a ma jẹ ẹrún awọn ọmọ labẹ tabili. 29 O si wi fun u pe, Nitori ọ̀rọ yi, mã lọ; ẹmi ẹ̀ṣu na ti jade kuro lara ọmọbinrin rẹ. 30 Nigbati o si pada wá si ile rẹ̀, o ri pe ẹmi èṣu na ti jade, ọmọbinrin rẹ̀ si sùn lori akete.

Jesu Wo Adití Akólòlò kan Sàn

31 O si tun lọ kuro li àgbegbe Tire on Sidoni, o wá si okun Galili larin àgbegbe Dekapoli. 32 Nwọn si mu enia kan wá sọdọ rẹ̀ ti etí rẹ̀ di, ti o si nkólolo; nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o gbé ọwọ́ rẹ̀ le e. 33 O si mu u kuro larin ijọ enia lọ si apakan, o si tẹ ika rẹ̀ bọ̀ ọ li etí, nigbati o tutọ́, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ li ahọn; 34 O si gbé oju soke wo ọrun, o kẹdùn, o si wi fun u pe, Efata, eyini ni, Iwọ ṣí. 35 Lojukanna, etì rẹ̀ si ṣí, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si nsọrọ ketekete. 36 O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ fun ẹnikẹni: ṣugbọn bi o ti npaṣẹ fun wọn to, bẹ̃ ni nwọn si nkokikí rẹ̀ to; 37 Ẹnu si yà wọn gidigidi rekọja, nwọn wipe, O ṣe ohun gbogbo daradara: o mu aditi gbọran, o si mu ki odi fọhun.

Marku 8

Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan

1 LI ọjọ wọnni nigbati ijọ enia pọ̀ gidigidi, ti nwọn ko si li onjẹ, Jesu pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, 2 Ãnu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn kò si li ohun ti nwọn o jẹ: 3 Bi emi ba si rán wọn lọ si ile wọn li ebi, ãrẹ̀ yio mu wọn li ọ̀na: nitori ninu wọn ti ọ̀na jijìn wá. 4 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si da a lohùn wipe, Nibo li a ó gbé ti le fi akara tẹ́ awọn enia wọnyi lọrùn li aginjù yi? 5 O si bi wọn lẽre, wipe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn si wipe, Meje. 6 O si paṣẹ ki awọn enia joko ni ilẹ: o si mu iṣu akara meje na, o dupẹ, o bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; nwọn si gbé e kalẹ niwaju awọn enia. 7 Nwọn si li ẹja kekeke diẹ: o si sure, o si ni ki a fi wọn siwaju wọn pẹlu. 8 Nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ agbọ̀n meje. 9 Awọn ti o jẹ ẹ to ìwọn ẹgbãji enia: o si rán wọn lọ. 10 Lojukanna, o si wọ̀ ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wá si apa ìha Dalmanuta.

Àwọn Farisi ń fẹ́ Àmì

11 Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò. 12 O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi. 13 O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji.

Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Ti Hẹrọdu

14 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn. 15 O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu. 16 Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Nitoriti awa kò mu akara lọwọ ni. 17 Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi? 18 Ẹnyin li oju ẹnyin kò si riran? ẹnyin li etí, ẹnyin kò si gbọran? ẹnyin kò si ranti? 19 Nigbati mo bu iṣu akara marun larin ẹgbẹdọgbọn enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wi fun u pe, Mejila. 20 Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje. 21 O si wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin?

Jesu Wo Afọ́jú kan Sàn ní Bẹtisaida

22 O si wá si Betsaida; nwọn si mu afọju kan wá sọdọ rẹ̀, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o fi ọwọ́ kàn a. 23 O si mu afọju na li ọwọ́, o si fà a jade lọ sẹhin ilu; nigbati o si tutọ́ si i loju, ti o si gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, o bi i lẽre bi o ri ohunkohun. 24 O si wòke, o si wipe, Mo ri awọn enia dabi igi, nwọn nrìn. 25 Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba. 26 O si rán a pada lọ si ile rẹ̀, wipe, Máṣe lọ si ilu, ki o má si sọ ọ fun ẹnikẹni ni ilu.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe

27 Jesu si jade, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ si awọn ileto Kesarea Filippi: o si bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre li ọna nwi fun wọn pe, Tali awọn enia nfi mi pè? 28 Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti: ẹlomiran si wipe Elijah; ṣugbọn awọn ẹlomiran wipe, Ọkan ninu awọn woli. 29 O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Peteru si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na. 30 O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ on fun ẹnikan.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

31 O si bẹ̀rẹ si ikọ́ wọn, pe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, a o si pa a, lẹhin ijọ mẹta yio si jinde. 32 O si sọ ọ̀rọ na ni gbangba. Peteru si mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi. 33 Ṣugbọn o yipada o si wò awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si ba Peteru wi, o ni, Kuro lẹhin mi, Satani: nitori iwọ ko ro ohun ti Ọlọrun bikoṣe ohun ti enia. 34 O si pè ijọ enia sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wi fun wọn pe Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. 35 Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là. 36 Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmi rẹ̀ nù? 37 Tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmi rẹ̀? 38 Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, ni iran panṣaga ati ẹlẹsẹ yi, on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ̀, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli mimọ́.

Marku 9

1 O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio tọ́ iku wò, titi nwọn o fi ri ti ijọba Ọlọrun yio fi de pẹlu agbara.

Jesu Para Dà lórí Òkè

2 Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn. 3 Aṣọ rẹ̀ si di didán, o si funfun gidigidi; afọṣọ kan li aiye kò le fọ̀ aṣọ fún bi iru rẹ̀. 4 Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ. 5 Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. 6 On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi. 7 Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. 8 Lojiji, nigbati nwọn si wò yika, nwọn ko si ri ẹnikan mọ́, bikoṣe Jesu nikan pẹlu ara wọn. 9 Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, o paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun ti nwọn ri fun ẹnikan, bikoṣe igbati Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú. 10 Nwọn si fi ọ̀rọ na pamọ́ sinu ara wọn, nwọn si mbi ara wọn lẽre, kili ajinde kuro ninu okú iba jẹ. 11 Nwọn si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Elijah ni yio tètekọ de? 12 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ, ni Elijah yio tètekọ, de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò; ati gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ̀ nipa ti Ọmọ-enia pe, ko le ṣaima jìya ohun pipọ, ati pe a o si kọ̀ ọ silẹ. 13 Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn si ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i, gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀.

Jesu Wo Ọmọ Tí Ó Ní Ẹ̀mí Èṣù Sàn

14 Nigbati nwọn si de ọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn ri ijọ enia pipọ lọdọ wọn, awọn akọwe si mbi wọn lẽre ọ̀ran. 15 Lọgan nigbati gbogbo enia si ri i, ẹnu si yà wọn gidigidi, nwọn si sare tọ ọ nwọn nki i. 16 O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn? 17 Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá; 18 Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e. 19 O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi. 20 Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu. 21 O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? o si wipe, Lati kekere ni. 22 Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ. 23 Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́. 24 Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ. 25 Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́. 26 On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú. 27 Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide. 28 Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade? 29 O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

30 Nwọn si ti ibẹ̀ kuro, nwọn si kọja larin Galili; on kò si fẹ ki ẹnikẹni mọ̀. 31 Nitori o kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ nwọn o si pa a; lẹhin igbati a ba si pa a tan, yio jinde ni ijọ kẹta. 32 Ṣugbọn ọ̀rọ na kò yé wọn, ẹ̀ru si ba wọn lati bi i lẽre.

Ta Ni Ẹni Tí Ó pọ̀jù Lọ?

33 O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na? 34 Ṣugbọn nwọn dakẹ: nitori nwọn ti mba ara wọn jiyan pe, tali ẹniti o pọ̀ju. 35 O si joko, o si pè awọn mejila na, o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba nfẹ ṣe ẹni iwaju, on na ni yio ṣe ẹni ikẹhin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn. 36 O si mu ọmọ kekere kan, o fi i sarin wọn; nigbati o si gbé e si apa rẹ̀, o wi fun wọn pe, 37 Ẹnikẹni ti o ba gbà ọkan ninu iru awọn ọmọ kekere wọnyi li orukọ mi, o gbà mi: ẹnikẹni ti o ba si gbà mi, ki iṣe emi li o gbà, ṣugbọn o gbà ẹniti o rán mi.

Ẹni Tí Kò Lòdì sí Wa, Tiwa ni

38 Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin: 39 Jesu si wipe, Ẹ máṣe da a lẹkun mọ́: nitori kò si ẹnikan ti yio ṣe iṣẹ agbara li orukọ mi, ti o si le yara sọ ibi si mi. 40 Nitori ẹniti ko ba kọ oju ija si wa, o wà ni iha tiwa. 41 Nitori ẹnikẹni ti o ba fi ago omi fun nyin mu li orukọ mi, nitoriti ẹnyin jẹ ti Kristi, lõtọ ni mo wi fun nyin, on kì yio padanù ère rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.

Ẹ̀tàn Sí Ẹ̀ṣẹ̀

42 Ẹnikẹni ti o ba si mu ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o sàn fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si sọ ọ sinu omi okun. 43 Bi ọwọ́ rẹ, ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ lọ si ibi iye, jù ki o li ọwọ mejeji ki o lọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku, 44 Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na kì si ikú. 45 Bi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsè, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akesẹ lọ si ibi ìye, jù ki o li ẹsẹ mejeji ki a gbé ọ sọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku, 46 Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú. 47 Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade: o sàn fun ọ ki o lọ si ijọba Ọlọrun li olojukan, jù ki o li oju mejeji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apadi, 48 Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú. 49 Nitoripe olukukuku li a o fi iná dùn, ati gbogbo ẹbọ li a o si fi iyọ̀ dùn. 50 Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba sọ agbara rẹ̀ nù, kili ẹ o fi mu u dùn? Ẹ ni iyọ̀ ninu ara nyin, ki ẹ si ma wà li alafia lãrin ara nyin.

Marku 10

Ìbéèrè Nípa Ìkọ̀sílẹ̀

1 O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn. 2 Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ? 3 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Aṣẹ kini Mose pa fun nyin? 4 Nwọn si wipe, Mose yọda fun wa lati kọ iwe ikọsilẹ fun u, ki a si fi i silẹ. 5 Jesu si da wọn lohùn, o si wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin li o ṣe kọ irú ofin yi fun nyin. 6 Ṣugbọn lati igba ti aiye ti ṣẹ, Ọlọrun da wọn ti akọ ti abo. 7 Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ ti yio si faramọ aya rẹ̀; 8 Awọn mejeji a si di ara kan: nitorina nwọn kì iṣe meji mọ́, bikoṣe ara kan. 9 Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn. 10 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tun bi i lẽre ọ̀ran kanna ninu ile. 11 O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba fi aya rẹ̀ silẹ, ti o ba si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga si i. 12 Bi obinrin kan ba si fi ọkọ rẹ̀ silẹ, ti a ba si gbé e ni iyawo fun ẹlomiran, o ṣe panṣaga.

Jesu Súre Fun Àwọn Ọmọde

13 Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá, ki o le fi ọwọ́ tọ́ wọn: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba awọn ti o gbé wọn wá wi. 14 Ṣugbọn nigbati Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun. 15 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio le wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù o ri. 16 O si gbé wọn si apa rẹ̀, o gbé ọwọ́ rẹ̀ le wọn, o si sure fun wọn.

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ kan

17 Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun? 18 Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun. 19 Iwọ sá mọ̀ ofin: Máṣe panṣaga, Máṣe pania, Máṣe jale, Máṣe jẹri eke, Máṣe rẹ-ni-jẹ, Bọwọ fun baba on iya rẹ. 20 O si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo nkan wọnyi li emi ti nkiyesi lati igba ewe mi wá. 21 Nigbana ni Jesu sì wò o, o fẹràn rẹ̀, o si wi fun u pe, Ohun kan li o kù ọ kù: lọ tà ohunkohun ti o ni ki o si fifun awọn talakà, iwọ ó si ni iṣura li ọrun: si wá, gbé agbelebu, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. 22 Inu rẹ̀ si bajẹ si ọ̀rọ̀ na, o si jade lọ ni ibinujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pipọ. 23 Jesu si wò yiká, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! 24 Ẹnu si yà awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọ̀rọ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu si tun dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ, yio ti ṣoro to fun awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! 25 O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. 26 Ẹnu si yà wọn rekọja, nwọn si mba ara wọn sọ wipe, Njẹ tali o ha le là? 27 Jesu si wò wọn o wipe, Enia li eyi ko le ṣe iṣe fun, ṣugbọn ki iṣe fun Ọlọrun: nitori ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun. 28 Nigbana ni Peteru bẹ̀rẹ si iwi fun u pe, Wo o, awa ti fi gbogbo nkan silẹ awa si ti tọ̀ ọ lẹhin. 29 Jesu si dahùn, o wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori mi, ati nitori ihinrere, 30 Ṣugbọn nisisiyi li aiye yi on o si gbà ọgọrọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun; 31 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

32 Nwọn si wà li ọ̀na nwọn ngoke lọ si Jerusalemu; Jesu si nlọ niwaju wọn: ẹnu si yà wọn; bi nwọn si ti ntọ̀ ọ lẹhin, ẹ̀ru ba wọn. O si tun mu awọn mejila, o bẹ̀rẹ si isọ gbogbo ohun ti a o ṣe si i fun wọn, 33 Wipe, Sá wo o, awa ngoke lọ si Jerusalemu, a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ; nwọn o si da a lẹbi ikú, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ: 34 Nwọn o si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn o si nà a, nwọn o si tutọ́ si i lara, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.

Jakọbu ati Johanu Bèèrè Ipò Ọlá

35 Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede si wá sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa nfẹ ki iwọ ki o ṣe ohunkohun ti awa ba bere lọwọ rẹ fun wa. 36 O si bi wọn lẽre pe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? 37 Nwọn si wi fun u pe, Fifun wa ki awa ki o le joko, ọkan li ọwọ́ ọtun rẹ, ati ọkan li ọwọ́ òsi rẹ, ninu ogo rẹ. 38 Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère: ẹnyin le mu ago ti emi mu? tabi ki a fi baptismu ti a fi baptisi mi baptisi nyin? 39 Nwọn si wi fun u pe, Awa le ṣe e. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin ó mu ago ti emi mu; ati baptismu ti a o fi baptisi mi li a o fi baptisi nyin: 40 Ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún mi ati li ọwọ́ òsi mi ki iṣe ti emi lati fi funni: bikoṣe fun awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ. 41 Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́, nwọn bẹ̀re si ibinu si Jakọbu ati Johanu. 42 Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ pe, awọn ti a nkà si olori awọn Keferi, a ma lò ipá lori wọn: ati awọn ẹni-nla wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. 43 Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ tobi lãrin nyin, on ni yio ṣe iranṣẹ nyin: 44 Ati ẹnikẹni ninu nyin ti o ba fẹ ṣe olori, on ni yio ṣe ọmọ-ọdọ gbogbo nyin. 45 Nitori Ọmọ-enia tikalarẹ̀ kò ti wá ki a ba mã ṣe iranṣẹ fun, bikoṣe lati mã ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada fun ọ̀pọlọpọ enia.

Jesu Wo Bartimẹu Afọ́jú Sàn

46 Nwọn si wá si Jeriko: bi o si ti njade kuro ni Jeriko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ awọn enia, Bartimeu afọju, ọmọ Timeu, joko lẹba ọ̀na, o nṣagbe. 47 Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Nasareti ni, o bẹ̀rẹ si ikigbe lohùn rara, wipe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 48 Ọpọlọpọ si ba a wipe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i jù bẹ̃ lọ pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 49 Jesu si dẹsẹ duro, o si paṣẹ pe ki a pè e wá. Nwọn si pè afọju na, nwọn wi fun u pe, Tùjuka, dide; o npè ọ. 50 O si bọ ẹ̀wu rẹ́ sọnù, o dide, o si tọ̀ Jesu wá. 51 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe fun ọ? Afọju na si wi fun u pe, Rabboni, ki emi ki o le riran. 52 Jesu si wi fun u pe, Mã lọ; igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. Lojukanna, o si riran, o si tọ̀ Jesu lẹhin li ọ̀na.

Marku 11

Jesu fi Ẹ̀yẹ wọ Jerusalẹmu

1 NIGBATI nwọn si sunmọ eti Jerusalemu, leti Betfage ati Betani, li òke Olifi, o rán meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, 2 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin: lojukanna bi ẹnyin ti nwọ̀ inu rẹ̀ lọ, ẹnyin ó si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn rì; ẹ tú u, ki é si fà a wá. 3 Bi ẹnikẹni ba si wi fun nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi? ẹ wipe, Oluwa ni fi ṣe; lojukanna yio si rán a wá sihinyi. 4 Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ na ti a so li ẹnu-ọ̀na lode ni ita gbangba; nwọn si tú u. 5 Awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe, ti ẹnyin fi ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ nì? 6 Nwọn si wi fun wọn gẹgẹ bi Jesu ti wi fun wọn: nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. 7 Nwọn si fà ọmọ kẹtẹkẹtẹ na tọ̀ Jesu wá, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin rẹ̀; on si joko lori rẹ̀. 8 Awọn pipọ si tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na: ati awọn miran ṣẹ́ ẹ̀ka igi, nwọn si fún wọn si ọ̀na. 9 Ati awọn ti nlọ niwaju, ati awọn ti mbọ̀ lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna; Olubukun li ẹniti o mbọ̀wá li orukọ Oluwa: 10 Olubukun ni ijọba ti mbọ̀wá, ijọba Dafidi, baba wa: Hosanna loke ọrun. 11 Jesu si wọ̀ Jerusalemu, ati tẹmpili. Nigbati o si wò ohun gbogbo yiká, alẹ sa ti lẹ tan, o si jade lọ si Betani pẹlu awọn mejila.

Jesu Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Gégùn-ún

12 Ni ijọ keji, nigbati nwọn ti Betani jade, ebi si npa a: 13 O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito. 14 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Ki ẹnikẹni má jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lai. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́ ọ.

Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà

15 Nwọn si wá si Jerusalemu: Jesu si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si tari tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. 16 Kò si jẹ ki ẹnikẹni ki o gbe ohun èlo kọja larin tẹmpili. 17 O si nkọ́ni, o nwi fun wọn pe, A ko ti kọwe rẹ̀ pe, Ile adura fun gbogbo orilẹ-ède li a o ma pè ile mi? ṣugbọn ẹnyin ti ṣọ di ihò awọn ọlọsà. 18 Awọn akọwe ati awọn olori alufa si gbọ́, nwọn si nwá ọ̀na bi nwọn o ti ṣe pa a run: nitori nwọn bẹ̀ru rẹ̀, nitori ẹnu yà gbogbo ijọ enia si ẹkọ́ rẹ̀. 19 Nigbati alẹ ba si lẹ, a jade kuro ni ilu.

Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Ó Gbẹ

20 Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo. 21 Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ. 22 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun. 23 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u. 24 Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin. 25 Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu. 26 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.

Ìbéèrè Nípa Àṣẹ tí Jesu Ń Lò

27 Nwọn si tún wá si Jerusalemu: bi o si ti nrìn kiri ni tẹmpili, awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbàgba, tọ̀ ọ wá, 28 Nwọn si wi fun u pe, Aṣẹ wo li o fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi lati mã ṣe nkan wọnyi? 29 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi ó bi nyin lẽre ọ̀rọ kan, ki ẹ si da mi lohùn, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi. 30 Baptismu Johanu lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? ẹ da mi lohùn. 31 Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni: on o wipe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́? 32 Ṣugbọn bi awa ba wipe, Lati ọdọ enia; nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitori gbogbo enia kà Johanu si woli nitõtọ. 33 Nwọn si dahùn wi fun Jesu pe, Awa kó mọ̀. Jesu si dahùn wi fun wọn pe, Emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

Marku 12

Òwe Nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà

1 O si bẹ̀rẹ si ifi owe ba wọn sọ̀rọ pe, ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si ṣọgba yi i ká, o si wà ibi ifunti waini, o si kọ́ ile-isọ si i, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si àjo. 2 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn oluṣọgba na, ki o le gbà ninu eso ọgba ajara na lọwọ awọn oluṣọgba. 3 Nwọn si mu u, nwọn lù u, nwọn si rán a pada lọwọ̀ ofo. 4 O si tún rán ọmọ-ọdọ miran si wọn, on ni nwọn si sọ okuta lù, nwọn sá a logbẹ́ li ori, nwọn si ran a lọ ni itiju. 5 O si tún rán omiran; eyini ni nwọn si pa: ati ọ̀pọ miran, nwọn lù miran, nwọn si pa miran. 6 Ṣugbọn o kù ọmọ rẹ̀ kan ti o ni, ti iṣe ayanfẹ rẹ̀, o si rán a si wọn pẹlu nikẹhin, o wipe, Nwọn ó ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. 7 Ṣugbọn awọn oluṣọgba wọnni wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ogún rẹ̀ yio si jẹ tiwa. 8 Nwọn si mu u, nwọn pa a, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu ọgba ajara na. 9 Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe? On o wá, yio si pa awọn oluṣọgba wọnni run, yio si fi ọgba ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn ẹlomiran. 10 Ẹnyin kò ha ti kà iwe-mimọ yi; Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ on na li o di pàtaki igun ile: 11 Eyi ni ìṣe Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? 12 Nwọn si nwá ọ̀na ati mu u, sugbọn nwọn si bẹ̀ru ijọ enia: nitori nwọn mọ̀ pe, awọn li o powe na mọ: nwọn si fi i silẹ, nwọn lọ.

Ìbéèrè nípa Owó-orí ti Ìjọba Kesari

13 Nwọn si rán awọn kan si i ninu awọn Farisi, ati ninu awọn ọmọ-ẹhin Herodu, lati fi ọ̀rọ rẹ̀ mu u. 14 Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? 15 Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u? Ṣugbọn Jesu mọ̀ agabagebe wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? ẹ mu owo-idẹ kan fun mi wá ki emi ki o wò o. 16 Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni. 17 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi.

Ìbéèrè Nípa Ajinde

18 Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe, 19 Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀. 20 Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ. 21 Eyi ekeji si ṣu u lopó, on si kú, bẹ̃li on kò si fi ọmọ silẹ: gẹgẹ bẹ̃ si li ẹkẹta. 22 Awọn mejeje si ṣu u lopó, nwọn kò si fi ọmọ silẹ: nikẹhin gbogbo wọn obinrin na kú pẹlu. 23 Njẹ li ajinde, nigbati nwọn ba jinde, aya tani yio ha ṣe ninu wọn? awọn mejeje li o sá ni i li aya? 24 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ki ha ṣe nitori eyi li ẹ ṣe ṣina, pe ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ, tabi agbara Ọlọrun? 25 Nitori nigbati nwọn o jinde kuro ninu okú, nwọn kò ni gbeyawo, bẹ̃ni nwọn kì yio sinni ni iyawo; ṣugbọn nwọn ó dabi awọn angẹli ti mbẹ li ọrun. 26 Ati niti awọn okú pe a o ji wọn dide: ẹnyin ko ti kà a ninu iwe Mose, bi Ọlọrun ti sọ fun u ninu igbẹ́, wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? 27 On kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikọse Ọlọrun awọn alãye: nitorina ẹnyin ṣìna gidigidi.

Òfin Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ

28 Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin? 29 Jesu si da a lohùn, wipe, Ekini ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. 30 Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: eyi li ofin ekini. 31 Ekeji si dabi rẹ̀, Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ko si si ofin miran, ti o tobi jù wọnyi lọ. 32 Akọwe na si wi fun u pe, Olukọni, o dara, otitọ li o sọ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; ko si si omiran bikoṣe on: 33 Ati ki a fi gbogbo àiya, ati gbogbo òye, ati gbogbo ọkàn, ati gbogbo agbara fẹ ẹ, ati ki a fẹ ọmọnikeji ẹni bi ara-ẹni, o jù gbogbo ẹbọ-sisun ati ẹbọ lọ. 34 Nigbati Jesu ri i pe o fi òye dahùn, o wi fun u pe, Iwọ kò jìna si ijọba Ọlọrun. Lẹhin eyini, kò si ẹnikan ti o jẹ bi i lẽre ohunkan mọ́.

Ìbéèrè Jesu Nípa Ọmọ Dafidi

35 Bi Jesu si ti nkọ́ni ni tẹmpili, o dahùn wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi iṣe? 36 Nitori Dafidi tikararẹ̀ wi nipa Ẹmi Mimọ́ pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. 37 Njẹ bi Dafidi tikararẹ̀ ba pè e li Oluwa; nibo li o si ti wa ijẹ ọmọ rẹ̀? Ọpọ ijọ enia si fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.

Jesu ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Akọ̀wé

38 O si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikíni li ọjà, 39 Ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi ase; 40 Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gigun fun aṣehàn: awọn wọnyi ni yio jẹbi pọ̀ju.

Ọrẹ Opó Kan

41 Jesu si joko kọjusi apoti iṣura, o si nwò bi ijọ enia ti nsọ owo sinu apoti iṣura: ọ̀pọ awọn ọlọrọ̀ si sọ pipọ si i. 42 Talakà opó kan si wá, o sọ owo idẹ wẹ́wẹ meji ti iṣe idameji owo-bàba kan sinu rẹ̀. 43 O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Talakà opó yi sọ sinu apoti iṣura jù gbogbo awọn ti o sọ sinu rẹ̀ lọ. 44 Nitori gbogbo nwọn sọ sinu rẹ̀ ninu ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rẹ̀ o sọ ohun gbogbo ti o ni si i, ani gbogbo ini rẹ̀.

Marku 13

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Wíwó Tẹmpili

1 BI o si ti nti tẹmpili jade, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wipe, Olukọni, wò irú okuta ati irú ile ti o wà nihinyi! 2 Jesu si dahùn wi fun u pe, Iwọ ri ile nla wọnyi? kì yio si okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrora

3 Bi o si ti joko lori òke Olifi ti o kọju si tẹmpili, Peteru ati Jakọbu, ati Johanu ati Anderu, bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, 4 Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi nigbati gbogbo nkan wọnyi yio ṣẹ? 5 Jesu si da wọn lohùn, o bẹ̀rẹ si isọ fun wọn pẹ, Ẹ mã kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ: 6 Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. 7 Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi. 8 Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. 9 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn. 10 A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède. 11 Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́. 12 Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn. 13 Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.

Àkókò Ìpọ́njú Ńlá

14 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke: 15 Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o máṣe sọkalẹ lọ sinu ile, bẹ̃ni ki o má si ṣe wọ̀ inu rẹ̀, lati mu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: 16 Ati ki ẹniti mbẹ li oko ki o maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. 17 Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmu fun ọmọ mu li ọjọ wọnni! 18 Ki ẹ si ma gbadura, ki sisá nyin ki o máṣe bọ́ si igba otutù. 19 Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si. 20 Bi ko si ṣe bi Oluwa ti ke ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là: ṣugbọn nitoriti awọn ayanfẹ ti o ti yàn, o ti ke ọjọ wọnni kuru. 21 Nitorina bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, wo o, Kristi mbẹ nihinyi; tabi, wo o, o mbẹ lọ́hun; ẹ máṣe gbà a gbọ́: 22 Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã. 23 Ṣugbọn ẹ kiyesara: wo o, mo sọ ohun gbogbo fun nyin tẹlẹ.

Dídé Ọmọ-Eniyan

24 Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn; 25 Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi. 26 Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo. 27 Nigbana ni yio si rán awọn angẹli rẹ̀, yio si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun aiye titi de ikangun ọrun.

Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́

28 Nisisiyi ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; Nigbati ẹ̀ka rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: 29 Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. 30 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi kì yio rekọja, titi a o fi mu gbogbo nkan wọnyi ṣẹ. 31 Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Nígbà Wo ni Àkókò Náà?

32 Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. 33 Ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã gbadura: nitori ẹnyin ko mọ̀ igbati akokò na yio de. 34 Nitori Ọmọ-enia dabi ọkunrin kan ti o lọ si àjo ti o jìna rére, ẹniti o fi ile rẹ̀ silẹ, ti o si fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iṣẹ olukuluku fun u, ti o si fi aṣẹ fun oluṣọna ki o mã ṣọna. 35 Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin ko mọ̀ igba ti bãle ile mbọ̀wá, bi li alẹ ni, tabi larin ọganjọ, tabi li akukọ, tabi li owurọ̀: 36 Pe, nigbati o ba de li ojijì, ki o máṣe ba nyin li oju orun. 37 Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mã ṣọna.

Marku 14

Ọ̀tẹ̀ Láti Pa Jesu

1 LẸHIN ọjọ meji ni ajọ irekọja, ati ti aiwukara: ati awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti fi ẹ̀tan mu u, ki nwọn ki o pa a. 2 Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia.

Obinrin kan Fi Òróró Kun Jesu ní Bẹtani

3 Nigbati o si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, bi o ti joko tì onjẹ, obinrin kan ti o ni oruba alabasta ororo ikunra nardi iyebiye, o wá, o si fọ́ orúba na, o si ndà a si i lori. 4 Awọn kan si wà ti inu wọn ru ninu ara wọn, nwọn si wipe, Nitori kili a ṣe nfi ororo ikunra yi ṣòfo? 5 A ba sá tà ororo ikunra yi jù ìwọn ọ̃dunrun owo idẹ lọ a ba si fifun awọn talakà. Nwọn si nkùn si i. 6 Ṣugbọn Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẽṣe ti ẹnyin fi mba a wi? iṣẹ rere li o ṣe si mì lara. 7 Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kó ni nigbagbogbo. 8 O ṣe eyi ti o le ṣe: o wá ṣiwaju lati fi oróro kùn ara mi fun sisinku mi. 9 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a o gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ̀ pẹlu li a o si rò ihin eyi ti obinrin yi ṣe lati fi ṣe iranti rẹ̀.

Judasi Ṣe Ètò láti Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀

10 Judasi Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila, si tọ̀ awọn olori alufa lọ, lati fi i le wọn lọwọ. 11 Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yọ̀, nwọn si ṣe ileri lati fun u li owo. O si nwá ọ̀na bi yio ti ṣe fi i le wọn lọwọ.

Àjọ̀dún Ìrékọjá

12 Li ọjọ kini ajọ aiwukara, nigbati nwọn npa ẹran irekọja, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a lọ ipèse silẹ, ki iwọ́ ki o le jẹ irekọja. 13 O si rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si ilu, ọkunrin kan ti nrù ìṣa omi yio pade nyin: ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin. 14 Ati ibikibi ti o ba gbé wọ̀, ki ẹnyin ki o wi fun bãle na pe, Olukọni wipe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? 15 On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ, ti a si pèse tẹlẹ; nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ dè wa. 16 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si jade lọ, nwọn wá si ilu, nwọn si ri i gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ. 17 Nigbati alẹ lẹ, o wá pẹlu awọn mejila. 18 Bi nwọn si ti joko ti nwọn njẹun, Jesu wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn, ani on na ti mba mi jẹun. 19 Nwọn si bẹ̀rẹ si ikãnu gidigidi, ati si ibi i lẽre lọkọ̃kan wipe, Emi ni bi? ekeji si wipe, Emi ni bi? 20 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Ọkan ninu awọn mejila ni, ti o ntọwọ bọ̀ inu awo pẹlu mi. 21 Nitõtọ Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a kò bí i.

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

22 Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun wọn, o wipe, Gbà, jẹ: eyiyi li ara mi. 23 O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀. 24 O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia. 25 Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o mu u ni titun ni ijọba Ọlọrun. 26 Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun

27 Jesu si wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru oni: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o lù oluṣọ agutan, a o si tú agbo agutan ká kiri. 28 Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili. 29 Ṣugbọn Peteru wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀, ṣugbọn emi kọ́. 30 Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, loni yi, ani li alẹ yi, ki akukọ ki o to kọ nigba meji, iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta. 31 Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.

Jesu Gbadura ní Gẹtisemani

32 Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura. 33 O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi. 34 O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna. 35 O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀. 36 O si wipe, Abba, Baba, ṣiṣe li ohun gbogbo fun ọ; mú ago yi kuro lori mi: ṣugbọn kì iṣe eyiti emi fẹ, bikoṣe eyiti iwọ fẹ, 37 O si wá, o ba wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ nsùn? iwọ kò le ṣọna ni wakati kan? 38 Ẹ mã ṣọna, kì ẹ si mã gbadura, ki ẹ má ba bọ́ sinu idẹwò. Lõtọ li ẹmí nfẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara. 39 O si tún pada lọ, o si gbadura, o nsọ ọ̀rọ kanna. 40 Nigbati o si pada wá, o tún bá wọn, nwọn nsùn, nitoriti oju wọn kún fun orun, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ èsi ti nwọn iba fifun u. 41 O si wá li ẹrinkẹta, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: o to bẹ̃, wakati na de; wo o, a fi Ọmọ-enia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ. 42 Ẹ dide, ki a ma lọ; wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.

Judasi Fi Jesu Fún Àwọn Ọ̀tá

43 Lojukanna, bi o si ti nsọ lọwọ, Judasi de, ọkan ninu awọn mejila, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà, pẹlu ọgọ, lati ọdọ olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbagba wá. 44 Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni; ẹ mu u, ki ẹ si ma fà a lọ li alafia. 45 Nigbati o de, o tọ̀ ọ lọ gan, o wipe, Olukọni, olukọni! o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 46 Nwọn si gbé ọwọ́ wọn le e, nwọn si mu u. 47 Ṣugbọn ọkan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ fà idà yọ, o si sá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí rẹ̀ kuro. 48 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? 49 Li ojojumọ li emi wà pẹlu nyin ni tẹmpili, ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si mu mi: ṣugbọn iwe-mimọ kò le ṣe alaiṣẹ. 50 Gbogbo wọn si fi i silẹ, nwọn si sá lọ. 51 Ọmọkunrin kan si ntọ̀ ọ lẹhin, ti o fi aṣọ ọgbọ bò ìhoho rẹ̀; awọn ọmọ-ogun si gbá a mu: 52 O si jọwọ aṣọ ọgbọ na lọwọ, o si sá kuro lọdọ wọn nihoho.

Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀

53 Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀. 54 Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána. 55 Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan. 56 Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan. 57 Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe, 58 Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe. 59 Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan. 60 Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? 61 Ṣugbọn Jesu dakẹ, ko si dahùn ohun kan. Olori alufa si tun bi i lẽre, o wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na, Ọmọ Olubukun nì? 62 Jesu si wipe, Emi ni: ẹnyin o si ri Ọmọ-enia joko li ọwọ́ ọtún agbara, yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. 63 Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, Ẹlẹri kili a si nwá? 64 Ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na: ẹnyin ti rò o si? Gbogbo wọn si da a lẹbi pe, o jẹbi ikú. 65 Awon miran si bẹ̀rẹ si itutọ́ si i lara, ati si ibò o loju, ati si ikàn a lẹṣẹ́, nwọn si wi fun u pe, Sọtẹlẹ: awọn onṣẹ si nfi atẹlẹ ọwọ́ wọn gbá a loju.

Peteru Sẹ́ Jesu

66 Bi Peteru si ti wà ni isalẹ li ãfin, ọkan ninu awọn ọmọbinrin olori alufa wá: 67 Nigbati o si ri ti Peteru nyána, o wò o, o si wipe, Iwọ pẹlu ti wà pẹlu Jesu ti Nasareti. 68 Ṣugbọn o sẹ́, wipe, Emi ko mọ̀, oyé ohun ti iwọ nwi kò tilẹ yé mi. O si jade lọ si iloro; akukọ si kọ. 69 Ọmọbinrin na si tún ri i, o si bẹ̀rẹ si iwi fun awọn ti o duro nibẹ̀ pe, Ọkan ninu wọn ni eyi. 70 O si tún sẹ́. O si pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tún wi fun Peteru pe, Lõtọ ni, ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe: nitoripe ara Galili ni iwọ, ède rẹ si jọ bẹ̃. 71 Ṣugbọn o bẹ̀rẹ si iré ati si ibura, wipe, Emi ko mọ̀ ọkunrin yi ẹniti ẹnyin nwi. 72 Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.

Marku 15

A Mú Jesu Lọ Siwaju Pilatu

1 ATI lojukanna li owurọ, awọn olori alufa jọ gbìmọ pẹlu awọn alàgba, ati awọn akọwe, ati gbogbo ajọ ìgbimọ, nwọn si dè Jesu, nwọn si mu u lọ, nwọn si fi i le Pilatu lọwọ. 2 Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i. 3 Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan. 4 Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ. 5 Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu. 6 Njẹ nigba ajọ na, on a ma dá ondè kan silẹ fun wọn, ẹnikẹni ti nwọn ba bere. 7 Ẹnikan si wà ti a npè ni Barabba, ẹniti a sọ sinu tubu pẹlu awọn ti o ṣọ̀tẹ pẹlu rẹ̀, awọn ẹniti o si pania pẹlu ninu ìṣọtẹ na. 8 Ijọ enia si bẹ̀rẹ si ikigbe soke li ohùn rara, nwọn nfẹ ki o ṣe bi on ti ima ṣe fun wọn ri. 9 Ṣugbọn Pilatu da wọn lohùn, wipe, Ẹnyin nfẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin? 10 On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ. 11 Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn. 12 Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju? 13 Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu. 14 Nigbana ni Pilatu si bi wọn lẽre, wipe, Eṣe? buburu kili o ṣe? Nwọn si kigbe soke gidigidi, wipe, Kàn a mọ agbelebu. 15 Pilatu si nfẹ se eyi ti o wù awọn enia, o da Barabba silẹ fun wọn. Nigbati o si nà Jesu tan, o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.

Àwọn Ọmọ-ogun Fi Jesu Ṣe Ẹlẹ́yà

16 Awọn ọmọ-ogun si fà a jade lọ sinu gbọ̀ngan, ti a npè ni Pretorioni; nwọn si pè gbogbo ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun jọ. 17 Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori; 18 Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! 19 Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u. 20 Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu.

A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

21 Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. 22 Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari. 23 Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a. 24 Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú. 25 Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu. 26 A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU. 27 Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. 28 Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. 29 Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, 30 Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. 31 Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. 32 Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.

Ikú Jesu

33 Nigbati o di wakati kẹfa, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. 34 Ni wakati kẹsan ni Jesu si kigbe soke li ohùn rara, wipe, Eloi, Eloi, lama sabaktani? itumọ eyi ti ijẹ, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? 35 Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, Wò o, o npè Elijah. 36 Ẹnikan si sare, o fi sponge bọ ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o fifun u mu, wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẹ jẹ ki a ma wò bi Elijah yio wá gbé e sọkalẹ. 37 Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ. 38 Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ. 39 Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe. 40 Awọn obinrin pẹlu si wà li òkere nwọn nwò: ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu kekere, ati ti Jose ati Salome; 41 (Awọn ẹniti, nigbati o wà ni Galili, ti nwọn ntọ̀ ọ lẹhin, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u;) ati ọ̀pọ obinrin miran pẹlu, ti o ba a goke wá si Jerusalemu.

Ìsìnkú Jesu

42 Nigbati alẹ si lẹ, nitoriti iṣe ọjọ ipalẹmọ, eyini ni, ọjọ ti o ṣiwaju ọjọ isimi, 43 Josefu ara Arimatea, ọlọlá ìgbimọ, ẹniti on tikalarẹ̀ pẹlu nreti ijọba Ọlọrun, o wá, o si wọle tọ̀ Pilatu lọ laifòya, o si tọrọ okú Jesu. 44 Ẹnu si yà Pilatu gidigidi, bi o ti kú na: o si pè balogun ọrún, o bi i lẽre bi igba ti o ti kú ti pẹ diẹ. 45 Nigbati o si mọ̀ lati ọdọ balọgun ọrún na, o si fi okú na fun Josefu. 46 O si rà aṣọ ọgbọ wá, o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ ọgbọ na dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu apata, o si yi okuta kan di ẹnu-ọ̀na ibojì na. 47 Ati Maria Magdalene, ati Maria iya Jose, ri ibi ti a gbé tẹ́ ẹ si.

Marku 16

Ajinde Jesu

1 NIGBATI ọjọ isimi si kọja, Maria Magdalene, ati Maria iya Jakọbu, ati Salome rà turari ki nwọn ba wá lati fi kùn u. 2 Ni kutukutu owurọ̀ ọjọ kini ọ̀sẹ, nwọn wá si ibi iboji nigbati õrùn bẹ̀rẹ si ilà. 3 Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Tani yio yi okuta kuro li ẹnu ibojì na fun wa? 4 Nigbati nwọn si wò o, nwọn ri pe a ti yi okuta na kuro: nitoripe o tobi gidigidi. 5 Nigbati nwọn si wọ̀ inu ibojì na, nwọn ri ọmọkunrin kan joko li apa ọtún, ti o wọ̀ agbada funfun; ẹ̀ru si ba wọn. 6 O si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin nwá Jesu ti Nasareti, ti a kàn mọ agbelebu: o jinde; kò si nihinyi: ẹ wò ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. 7 Ṣugbọn ẹ lọ, ki ẹ si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati Peteru pe, o ṣaju nyin lọ si Galili: nibẹ̀ li ẹnyin ó gbe ri i, bi o ti wi fun nyin. 8 Nwọn si jade lọ kánkan, nwọn si sá kuro ni ibojì; nitoriti nwọn nwarìri, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi: bẹ̃ni nwọn ko wi ohunkohun fun ẹnikan; nitoripe ẹ̀ru ba wọn. 9 Nigbati Jesu jinde li owurọ̀ kutukutu ni ijọ kini ọ̀sẹ, o kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, lara ẹniti o ti lé ẹmi èṣu meje jade. 10 On si lọ sọ fun awọn ti o ti mba a gbé, bi nwọn ti ngbàwẹ, ti nwọn si nsọkun. 11 Ati awọn, nigbati nwọn si gbọ́ pe o ti di alãye, ati pe, on si ti ri i, nwọn kò gbagbọ.

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn Meji

12 Lẹhin eyini, o si fi ara hàn fun awọn meji ninu wọn li ọna miran, bi nwọn ti nrìn li ọ̀na, ti nwọn si nlọ si igberiko. 13 Nwọn si lọ isọ fun awọn iyokù: nwọn kò si gbà wọn gbọ́ pelu.

Jesu Fara Han Àwọn Mọkanla

14 Lẹhinna o si fi ara hàn fun awọn mọkanla bi nwọn ti joko tì onje, o si ba aigbagbọ́ ati lile àiya wọn wi, nitoriti nwọn ko gbà awọn ti o ti ri i gbọ́ lẹhin igbati o jinde. 15 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda. 16 Ẹniti o ba gbagbọ́, ti a ba si baptisi rẹ̀ yio là; ṣugbọn ẹniti kò ba gbagbọ́ yio jẹbi. 17 Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọ̀rọ; 18 Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ́ le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.

Ìgòkè-Re-Ọ̀run Ti Jesu

19 Bẹ̃ni nigbati Oluwa si ti ba wọn sọ̀rọ tan, a si gbà a lọ soke ọrun, o si joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun. 20 Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, Oluwa si mba wọn ṣiṣẹ, o si nfi idi ọ̀rọ na kalẹ, nipa àmi ti ntẹ̀le e. Amin.

Luku 1

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju sí Tiofilu

1 NIWỌNBI ọ̀pọ enia ti dawọle e lati tò ìhin wọnni jọ lẹsẹsẹ, eyiti o ti gbilẹ ṣinṣin lãrin wa, 2 Ani gẹgẹ bi awọn ti o ṣe oju wọn lati ibẹrẹ, ti nwọn si jasi iranṣẹ ọrọ na, ti fi le wa lọwọ; 3 O si yẹ fun mi pẹlu, lati kọwe si ọ lẹsẹsẹ bi mo ti wadi ohun gbogbo kinikini si lati ipilẹsẹ, Teofilu ọlọla jùlọ, 4 Ki iwọ ki o le mọ̀ ọtitọ ohun wọnni, ti a ti kọ́ ọ.

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi

5 Nigba ọjọ Herodu ọba Judea, alufa kan wà, ni ipa ti Abia, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Sakariah: aya rẹ̀ si ṣe ọkan ninu awọn ọmọbinrin Aaroni, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Elisabeti. 6 Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrìn ni gbogbo ofin on ìlana Oluwa li ailẹgan. 7 Ṣugbọn nwọn kò li ọmọ, nitoriti Elisabeti yàgan, awọn mejeji si di arugbo. 8 O si ṣe, nigbati o nṣe iṣẹ alufa niwaju Ọlọrun ni ipa iṣẹ́ tirẹ̀, 9 Bi iṣe awọn alufa, ipa tirẹ̀ ni ati ma fi turari jóna, nigbati o ba wọ̀ inu tẹmpili Oluwa lọ. 10 Gbogbo ijọ awọn enia si ngbadura lode li akokò sisun turari. 11 Angẹli Oluwa kan si fi ara hàn a, o duro li apa ọtún pẹpẹ turari. 12 Nigbati Sakariah si ri i, ori rẹ̀ wúle, ẹ̀ru si ba a. 13 Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu. 14 Iwọ o si li ayọ̀ ati inu didùn: enia pipọ yio si yọ̀ si ibí rẹ̀. 15 Nitori on o pọ̀ niwaju Oluwa, kì yio si mu ọti-waini, bẹ̃ni kì yio si mu ọti-lile; yio si kún fun Ẹmi Mimọ́ ani lati inu iya rẹ̀ wá. 16 On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israeli si Oluwa Ọlọrun wọn. 17 Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa. 18 Sakariah si wi fun angẹli na pe, Àmi wo li emi o fi mọ̀ eyi? Emi sá di àgba, ati Elisabeti aya mi si di arugbo. 19 Angẹli na si dahùn o wi fun u pe, Emi ni Gabrieli, ti ima duro niwaju Ọlọrun; emi li a rán wá lati sọ fun ọ, ati lati mu ìhin ayọ̀ wọnyi fun ọ wá. 20 Si kiyesi i, iwọ o yadi, iwọ kì yio si le fọhun, titi ọjọ na ti nkan wọnyi yio fi ṣẹ, nitori iwọ ko gbà ọ̀rọ mi gbọ́ ti yio ṣẹ li akokò wọn. 21 Awọn enia si duro dè Sakariah, ẹnu si yà wọn nitoriti o pẹ ninu tẹmpili. 22 Nigbati o si jade, kò le fọhun si wọn: nwọn si woye pe o ri iran ninu tẹmpili: nitoriti o nṣe apẹrẹ si wọn, o si yà odi. 23 O si ṣe, nigbati ọjọ iṣẹ isin rẹ̀ pe, o lọ si ile rẹ̀. 24 Lẹhin ọjọ wọnyi ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyun, o si fi ara rẹ̀ pamọ́ li oṣù marun, o ni, 25 Bayi li Oluwa ṣe fun mi li ọjọ ti o ṣijuwò mi, lati mu ẹ̀gan mi kuro lọdọ araiye.

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìbí Jesu

26 Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti, 27 Si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan, ti a npè ni Josefu, ti idile Dafidi; orukọ wundia na a si ma jẹ Maria. 28 Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin. 29 Ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò lelẹ nitori ọ̀rọ na, o si rò ninu ara rẹ̀ pe, irú kíki kili eyi. 30 Angẹli na si wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun. 31 Sá si kiyesi i, iwọ o lóyun ninu rẹ, iwọ o si bí ọmọkunrin kan, iwọ o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU. 32 On o pọ̀, Ọmọ Ọgá-ogo julọ li a o si ma pè e: Oluwa Ọlọrun yio si fi itẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun u: 33 Yio si jọba ni ile Jakọbu titi aiye; ijọba rẹ̀ ki yio si ni ipẹkun. 34 Nigbana ni Maria wi fun angẹli na pe, Eyi yio ha ti ṣe ri bẹ̃, nigbati emi kò ti mọ̀ ọkunrin? 35 Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e. 36 Si kiyesi i, Elisabeti ibatan rẹ, on pẹlu si lóyun ọmọkunrin kan li ogbologbo rẹ̀: eyi si li oṣu kẹfa fun ẹniti a npè li agàn. 37 Nitori kò si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe. 38 Maria si wipe, Wò ọmọ-ọdọ Oluwa; ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Angẹli na si fi i silẹ lọ.

Maria Lọ Bẹ Elisabẹti Wò

39 Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda; 40 O si wọ̀ ile Sakariah lọ o si ki Elisabeti. 41 O si ṣe, nigbati Elisabeti gbọ́ kikí Maria, ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabeti si kún fun Ẹmí Mimọ́: 42 O si ke li ohùn rara, o si wipe, Alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun-fun si ni fun ọmọ inu rẹ. 43 Nibo si li eyi ti wá ba mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wá? 44 Sawò o, bi ohùn kikí rẹ ti bọ́ si mi li etí, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀. 45 Alabukun-fun si li ẹniti o gbagbọ́: nitori nkan wọnyi ti a ti sọ fun u lati ọdọ Oluwa wá yio ṣẹ.

Maria Kọ Orin Ìyìn

46 Maria si dahùn, o ni, Ọkàn mi yìn Oluwa logo, 47 Ẹmí mi si yọ̀ si Ọlọrun Olugbala mi. 48 Nitoriti o ṣijuwò ìwa irẹlẹ ọmọbinrin ọdọ rẹ̀: sá wò o, lati isisiyi lọ gbogbo iran enia ni yio ma pè mi li alabukunfun. 49 Nitori ẹniti o li agbara ti ṣe ohun ti o tobi fun mi; mimọ́ si li orukọ rẹ̀. 50 Anu rẹ̀ si mbẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ lati irandiran. 51 O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn. 52 O ti mu awọn alagbara kuro lori itẹ́ wọn, o si gbé awọn talakà leke. 53 O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa; o si rán awọn ọlọrọ̀ pada lọwọ ofo. 54 O ti ràn Israeli ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọwọ, ni iranti ãnu rẹ̀; 55 Bi o ti sọ fun awọn baba wa, fun Abrahamu, ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lailai. 56 Maria si ba a joko niwọn oṣù mẹta, o si pada lọ si ile rẹ̀. 57 Ọjọ Elisabeti pe wayi ti yio bí; o si bí ọmọkunrin kan.

Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi

58 Ati awọn aladugbo, ati awọn ibatan rẹ̀ gbọ́ bi Oluwa ti ṣe ãnu nla fun u; nwọn si ba a yọ̀. 59 O si ṣe, ni ijọ kẹjọ nwọn wá lati kọ ọmọ na nila; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Sakariah, gẹgẹ bi orukọ baba rẹ̀. 60 Iya rẹ̀ si dahùn, o ni Bẹ̃kọ; bikoṣe Johanu li a o pè e. 61 Nwọn si wi fun u pe, Kò si ọkan ninu awọn ará rẹ ti a npè li orukọ yi. 62 Nwọn si ṣe apẹrẹ si baba rẹ̀, bi o ti nfẹ ki a pè e. 63 O si bère walã, o kọ, wipe, Johanu li orukọ rẹ̀. Ẹnu si yà gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ si ṣí lọgan, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si sọ̀rọ, o si nyìn Ọlọrun. 65 Ẹ̀ru si ba gbogbo awọn ti mbẹ li àgbegbe wọn: a si rohin gbogbo nkan wọnyi ká gbogbo ilẹ òke Judea. 66 Gbogbo awọn ti o gbọ́ si tò o sinu ọkàn wọn, nwọn nwipe, Irú ọmọ kili eyi yio jẹ! Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.

Sakaraya Sọ Àsọtẹ́lẹ̀

67 Sakariah baba rẹ̀ si kún fun Ẹmí Mimọ́, o si sọtẹlẹ, o ni, 68 Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israeli; nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rẹ̀ nide, 69 O si ti gbé iwo igbala soke fun wa ni ile Dafidi ọmọ-ọdọ rẹ̀; 70 Bi o ti wi li ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́, ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀: 71 Pe, a o gbà wa là lọwọ awọn ọtá wa, ati lọwọ gbogbo awọn ti o korira wa; 72 Lati ṣe ãnu ti o ti leri fun awọn baba wa, ati lati ranti majẹmu rẹ̀ mimọ́, 73 Ara ti o ti bú fun Abrahamu baba wa, 74 Pe on o fifun wa, lati gbà wa lọwọ awọn ọtá wa, ki awa ki o le ma sìn i laifòya, 75 Ni mimọ́ ìwa ati li ododo niwaju rẹ̀, li ọjọ aiye wa gbogbo. 76 Ati iwọ, ọmọ, woli Ọgá-ogo li a o ma pè ọ: nitori iwọ ni yio ṣaju Oluwa lati tún ọ̀na rẹ̀ ṣe; 77 Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn, 78 Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa, 79 Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia. 80 Ọmọ na si dàgba, o si le li ọkàn, o si wà ni ijù titi o fi di ọjọ ifihàn rẹ̀ fun Israeli.

Luku 2

Ìbí Jesu

1 O SI ṣe li ọjọ wọnni, aṣẹ ti ọdọ Kesari Augustu jade wá pe, ki a kọ orukọ gbogbo aiye sinu iwe. 2 (Eyi ni ikọsinu-iwe ikini ti a ṣe nigbati Kireniu fi jẹ Bãlẹ Siria.) 3 Gbogbo awọn enia si lọ lati kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe, olukuluku si ilu ara rẹ̀. 4 Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npè ni Betlehemu; nitoriti iran ati idile Dafidi ni iṣe, 5 Lati kọ orukọ rẹ̀, pẹlu Maria aya rẹ̀ afẹsọna, ti o tobi fun oyún. 6 O si ṣe, nigbati nwọn wà nibẹ̀, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí. 7 O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro. 8 Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé. 9 Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi. 10 Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo. 11 Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa. 12 Eyi ni yio si ṣe àmi fun nyin; ẹnyin ó ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọja wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran. 13 Ọpọlọpọ ogun ọrun si yọ si angẹli na li ojijì, nwọn nyìn Ọlọrun, wipe, 14 Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia. 15 O si ṣe, nigbati awọn angẹli na pada kuro lọdọ wọn lọ si ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn sọ pe, Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa. 16 Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. 17 Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. 18 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá. 19 Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀. 20 Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ́ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn.

A Sọ Jesu Lórúkọ

21 Nigbati ijọ mẹjọ si pé lati kọ ọmọ na nila, nwọn pè orukọ rẹ̀ ni JESU, bi a ti sọ ọ tẹlẹ lati ọdọ angẹli na wá ki a to lóyun rẹ̀ ninu. 22 Nigbati ọjọ iwẹnu Maria si pé gẹgẹ bi ofin Mose, nwọn gbé Jesu wá si Jerusalemu lati fi i fun Oluwa; 23 (Bi a ti kọ ọ sinu ofin Oluwa pe, Gbogbo ọmọ ọkunrin ti o ṣe akọbi, on li a o pè ni mimọ́ fun Oluwa;) 24 Ati lati rubọ gẹgẹ bi eyi ti a wi ninu ofin Oluwa, Àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji. 25 Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e. 26 A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa. 27 O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin. 28 Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni, 29 Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: 30 Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na, 31 Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo; 32 Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ. 33 Ẹnu si yà Josefu ati iya rẹ̀ si nkan ti a nsọ si i wọnyi. 34 Simeoni si sure fun wọn, o si wi fun Maria iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, a gbé ọmọ yi kalẹ fun iṣubu ati idide ọ̀pọ enia ni Israeli; ati fun àmi ti a nsọ̀rọ òdi si; 35 (Idà yio si gún iwọ na li ọkàn pẹlu,) ki a le fi ironu ọ̀pọ ọkàn hàn. 36 Ẹnikan si mbẹ, Anna woli, ọmọbinrin Fanueli, li ẹ̀ya Aseri: ọjọ ogbó rẹ̀ pọ̀, o ti ba ọkọ gbé li ọdún meje lati igba wundia rẹ̀ wá; 37 O si ṣe opó ìwọn ọdún mẹrinlelọgọrin, ẹniti kò kuro ni tẹmpili, o si nfi àwẹ ati adura sìn Ọlọrun lọsán ati loru. 38 O si wọle li akokò na, o si dupẹ fun Oluwa pẹlu, o si sọ̀rọ rẹ̀ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalemu.

Àwọn Òbí Jesu Gbé e Pada Lọ sí Nasarẹti

39 Nigbati nwọn si ti ṣe nkan gbogbo tan gẹgẹ bi ofin Oluwa, nwọn pada lọ si Galili, si Nasareti ilu wọn. 40 Ọmọ na si ndàgba, o si nlagbara, o si kún fun ọgbọn: ore-ọfẹ Ọlọrun si mbẹ lara rẹ̀.

Jesu lọ sí Tẹmpili Nígbà Ọ̀dọ́ Rẹ̀

41 Awọn õbi rẹ̀ a si mã lọ si Jerusalemu li ọdọdún si ajọ irekọja. 42 Nigbati o si di ọmọ ọdún mejila, nwọn goke lọ si Jerusalemu gẹgẹ bi iṣe ajọ na. 43 Nigbati ọjọ wọn si pé bi nwọn ti npada bọ̀, ọmọ na Jesu duro lẹhin ni Jerusalemu; Josefu ati iya rẹ̀ kò mọ̀. 44 Ṣugbọn nwọn ṣebi o wà li ẹgbẹ èro, nwọn rìn ìrin ọjọ kan; nwọn wá a kiri ninu awọn ará ati awọn ojulumọ̀ wọn. 45 Nigbati nwọn kò si ri i, nwọn pada si Jerusalemu, nwọn nwá a kiri. 46 O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri i ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ ti wọn, o si mbi wọn lẽre. 47 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ fun oyé ati idahùn rẹ̀. 48 Nigbati nwọn si ri i, hà ṣe wọn: iya rẹ̀ si bi i pe, Ọmọ, ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃? sawò o, baba rẹ ati emi ti nfi ibinujẹ wá ọ kiri. 49 O si dahùn wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá mi kiri? ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi? 50 Ọrọ ti o sọ kò si yé wọn. 51 O si ba wọn sọkalẹ lọ si Nasareti, o si fi ara balẹ fun wọn: ṣugbọn iya rẹ̀ pa gbogbo nkan wọnyi mọ́ ninu ọkàn rẹ̀. 52 Jesu si npọ̀ li ọgbọ́n, o si ndàgba, o si wà li ojurere li ọdọ Ọlọrun ati enia.

Luku 3

Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi

1 LI ọdún kẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigbati Pontiu Pilatu jẹ Bãlẹ, Judea, ti Herodu si jẹ tetrarki Galili, Filippi arakunrin rẹ̀ si jẹ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ tetrarki Abilene, 2 Ti Anna on Kaiafa nṣe olori awọn alufa, nigbana li ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Johanu ọmọ Sakariah wá ni ijù. 3 O si wá si gbogbo ilẹ ìha Jordani, o nwasu baptismu ironupiwada fun imukuro ẹ̀ṣẹ; 4 Bi a ti kọ ọ ninu iwe ọ̀rọ woli Isaiah pe, Ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ mu ipa-ọna rẹ̀ tọ́. 5 Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna; 6 Gbogbo enia ni yio si ri igbala Ọlọrun. 7 Nigbana li o wi fun ọ̀pọ awọn enia ti o wá lati baptisi lọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin iran paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀? 8 Nitorina ki ẹnyin ki o so eso ti o yẹ fun ironupiwada, ki ẹ má si ṣe bẹ̀rẹ si iwi ninu ara nyin pe, awa ni Abrahamu ni baba: ki emi ki o wi fun nyin, Ọlọrun le gbe ọmọ dide fun Abrahamu ninu okuta wọnyi. 9 Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná. 10 Awọn enia si mbi i pe, Kini ki awa ki o ha ṣe? 11 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu. 12 Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe? 13 O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́. 14 Awọn ọmọ-ogun si bère lọdọ rẹ̀, pe, Ati awa, kili awa o ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe huwa ipá si ẹnikẹni, ki ẹ má si ṣe rẹ ẹnikẹni jẹ; ki owo onjẹ nyin to nyin. 15 Bi awọn enia si ti nreti, ti gbogbo wọn si nrò ninu ara wọn nitori Johanu, bi on ni Kristi bi on kọ́; 16 Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin: 17 Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, lati gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, ki o si kó alikama rẹ̀ sinu aká; ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun. 18 Ohun pipọ pẹlu li o si wasu fun awọn enia ni ọrọ iyanju rẹ̀. 19 Ṣugbọn Herodu tetrarki, ti o bawi nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀, ati nitori ohun buburu gbogbo ti Herodu ti ṣe, 20 O fi eyi pari gbogbo rẹ̀ niti o fi Johanu sinu tubu.

Johanu Ṣe Ìrìbọmi fún Jesu

21 Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀, 22 Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Ìrandíran Jesu

23 Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli, 24 Ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi, ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Janna, ti iṣe ọmọ Josefu, 25 Ti iṣe ọmọ Mattatai, ti iṣe ọmọ Amosi, ti iṣe ọmọ Naumu, ti iṣe ọmọ Esli, ti iṣe ọmọ Naggai, 26 Ti iṣe ọmọ Maati, ti iṣe ọmọ Mattatia, ti iṣe ọmọ Simei, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Juda, 27 Ti iṣe ọmọ Joanna, ti iṣe ọmọ Resa, ti iṣe ọmọ Sorobabeli, ti iṣe ọmọ Salatieli, ti iṣe ọmọ Neri, 28 Ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Addi, ti iṣe ọmọ Kosamu, ti iṣe ọmọ Elmodamu, ti iṣe ọmọ Eri, 29 Ti iṣe ọmọ Jose, ti iṣe ọmọ Elieseri, ti iṣe ọmọ Jorimu, ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi, 30 Ti iṣe ọmọ Simeoni, ti iṣe ọmọ Juda, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Jonani, ti iṣe ọmọ Eliakimu, 31 Ti iṣe ọmọ Melea, ti iṣe ọmọ Menani, ti iṣe ọmọ Mattata, ti iṣe ọmọ Natani, ti iṣe ọmọ Dafidi, 32 Ti iṣe ọmọ Jesse, ti iṣe ọmọ Obedi, ti iṣe ọmọ Boasi, ti iṣe ọmọ Salmoni, ti iṣe ọmọ Naassoni, 33 Ti iṣe ọmọ Aminadabu, ti iṣe ọmọ Aramu, ti iṣe ọmọ Esromu, ti iṣe ọmọ Faresi, ti iṣe ọmọ Juda, 34 Ti iṣe ọmọ Jakọbu, ti iṣe ọmọ Isaaki, ti iṣe ọmọ Abrahamu, ti iṣe ọmọ Tera, ti iṣe ọmọ Nakoru, 35 Ti iṣe ọmọ Saruku, ti iṣe ọmọ Ragau, ti iṣe ọmọ Faleki, ti iṣe ọmọ Eberi, ti iṣe ọmọ Sala, 36 Ti iṣe ọmọ Kainani, ti iṣe ọmọ Arfaksadi, ti iṣe ọmọ Semu, ti iṣe ọmọ Noa, ti iṣe ọmọ Lameki, 37 Ti iṣe ọmọ Metusala, ti iṣe ọmọ Enoku, ti iṣe ọmọ Jaredi, ti iṣe ọmọ Maleleeli, ti iṣe ọmọ Kainani, 38 Ti iṣe ọmọ Enosi, ti iṣe ọmọ Seti, ti iṣe ọmọ Adamu, ti iṣe ọmọ Ọlọrun.

Luku 4

Ìdánwò Jesu

1 JESU si kún fun Ẹmí Mimọ́, o pada ti Jordani wá, a si ti ọwọ́ Ẹmí dari rẹ̀ si ijù; 2 Ogoji ọjọ li a fi dán a wò lọwọ Èṣu. Kò si jẹ ohunkohun li ọjọ wọnni: nigbati nwọn si pari, lẹhinna li ebi wá npa a. 3 Eṣu si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ fun okuta yi ki o di akara. 4 Jesu si dahùn wi fun u pe, A ti kọwe rẹ pe, Enia kì yio wà lãye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ Ọlọrun. 5 Èṣu si mu u re ori òke giga, o si fi gbogbo ilẹ-ọba aiye hàn a ni iṣẹju kan. 6 Èṣu si wi fun u pe, Iwọ li emi o fi gbogbo agbara yi ati ogo wọn fun: gbogbo rẹ̀ li a sá ti fifun mi; ẹnikẹni ti o ba si wù mi, emi a fi i fun. 7 Njẹ bi iwọ ba foribalẹ fun mi, gbogbo rẹ̀ ni yio jẹ tirẹ. 8 Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kuro lẹhin mi, Satani, nitoriti a kọwe rẹ̀ pe, Iwọ foribalẹ fun Oluwa Ọlọrun rẹ, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o si ma sìn. 9 O si mu u lọ si Jerusalemu, o si gbé e le ṣonṣo tẹmpili, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ lati ihinyi lọ: 10 A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, lati ma ṣe itọju rẹ: 11 Ati pe li ọwọ́ wọn ni nwọn o gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. 12 Jesu si dahùn o wi fun u pe, A ti sọ pe, Iwọ kò gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò. 13 Nigbati Èṣu si pari idanwò na gbogbo, o fi i silẹ lọ di sã kan.

Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Galili

14 Jesu si fi agbara Ẹmí pada wá si Galili: okikí rẹ̀ si kàn kalẹ ni gbogbo àgbegbe ti o yiká. 15 O si nkọni ninu sinagogu wọn; a nyìn i logo lati ọdọ gbogbo awọn enia wá.

Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu

16 O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe. 17 A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si ṣí iwe na, o ri ibiti a gbé kọ ọ pe, 18 Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ. 19 Lati kede ọdún itẹwọgba Oluwa. 20 O si pa iwe na de, o tun fi i fun iranṣẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ. 21 O si bẹ̀rẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni Iwe-mimọ yi ṣẹ li etí nyin. 22 Gbogbo wọn si jẹri rẹ̀, ha si ṣe wọn si ọ̀rọ ore-ọfẹ ti njade li ẹnu rẹ̀. Nwọn si wipe, Ọmọ Josefu kọ́ yi? 23 O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o pa owe yi si mi pe, Oniṣegun, wò ara rẹ sàn: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapernaumu, ṣe e nihinyi pẹlu ni ilẹ ara rẹ. 24 O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si woli ti a tẹwọgbà ni ilẹ baba rẹ̀. 25 Ṣugbọn mo wi fun nyin nitõtọ, opó pipọ li o wà ni Israeli nigba ọjọ woli Elijah, nigbati ọrun fi sé li ọdún mẹta on oṣù mẹfa, nigbati ìyan nla fi mu ká ilẹ gbogbo; 26 Kò si si ẹnikan ninu wọn ti a rán Elijah si, bikoṣe si obinrin opó kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni. 27 Ati adẹtẹ̀ pipọ ni mbẹ ni Israeli nigba woli Eliṣa; kò si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ́, bikoṣe Naamani ara Siria. 28 Nigbati gbogbo awọn ti o wà ninu sinagogu gbọ́ nkan wọnyi, inu ru wọn ṣùṣù, 29 Nwọn si dide, nwọn tì i sode si ẹhin ilu, nwọn si fà a lọ si bèbe òke nibiti nwọn gbé tẹ̀ ilu wọn do, ki nwọn ba le tari rẹ̀ li ogedengbe. 30 Ṣugbọn o kọja larin wọn, o ba tirẹ̀ lọ.

Ọkunrin Tí Ó Ní Ẹ̀mí Èṣù

31 O si sọkalẹ wá si Kapernaumu, ilu kan ni Galili, o si nkọ́ wọn li ọjọ isimi. 32 Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitori taṣẹ-taṣẹ li ọ̀rọ rẹ̀. 33 Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu, ẹniti o li ẹmi aimọ́, o kigbe li ohùn rara, 34 O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun. 35 Jesu si ba a wi, o ni, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade lara rẹ̀. Nigbati ẹmí eṣu na si gbé e ṣanlẹ li awujọ, o jade kuro lara rẹ̀, kò si pa a lara. 36 Hà si ṣe gbogbo wọn nwọn si mba ara wọn sọ, wipe, Ọ̀rọ kili eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara li o fi ba awọn ẹmi aimọ́ wi, nwọn si jade kuro. 37 Okikí rẹ̀ si kàn nibi gbogbo li àgbegbe ilẹ na yiká.

Jesu Wo Ọpọlọpọ Eniyan Sàn

38 Nigbati o si dide kuro ninu sinagogu, o si wọ̀ ile Simoni lọ; ibà si ti dá iya aya Simoni bulẹ; nwọn si bẹ̀ ẹ nitori rẹ̀. 39 O si duro tirisi i, o ba ibà na wi; ibà si jọwọ rẹ̀ lọwọ: o si dide lọgan, o nṣe iranṣẹ fun wọn. 40 Nigbati õrùn si nwọ̀, gbogbo awọn ẹniti o ni olokunrun ti o li arunkarun, nwọn mu wọn tọ̀ ọ wá; o si fi ọwọ́ le olukuluku wọn, o si mu wọn larada. 41 Awọn ẹmi eṣu si jade lara ẹni pipọ pẹlu, nwọn nkigbe, nwọn si nwipe, Iwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọrun. O si mba wọn wi, kò si jẹ ki nwọn ki o fọhun: nitoriti nwọn mọ̀ pe Kristi ni iṣe.

Jesu Ń Waasu Kiri

42 Nigbati ilẹ si mọ́, o dide lọ si ibi ijù: ijọ enia si nwá a kiri, nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si da a duro, nitori ki o má ba lọ kuro lọdọ wọn. 43 Ṣugbọn o si wi fun wọn pe, Emi kò le ṣaima wasu ijọba Ọlọrun fun ilu miran pẹlu: nitorina li a sá ṣe rán mi. 44 O si nwasu ninu sinagogu ti Galili.

Luku 5

Jesu Pe Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Rẹ̀ Àkọ́kọ́

1 O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti, 2 O ri ọkọ̀ meji ti nwọn gún leti adagun: ṣugbọn awọn apẹja sọkalẹ kuro ninu wọn, nwọn nfọ̀ àwọn wọn. 3 O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na. 4 Bi o si ti dakẹ ọ̀rọ isọ, o wi fun Simoni pe, Tì si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ̀. 5 Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ. 6 Nigbati nwọn si ti ṣe eyi, nwọn kó ọpọlọpọ ẹja: àwọn wọn si ya. 7 Nwọn si ṣapẹrẹ si ẹgbẹ wọn, ti o wà li ọkọ̀ keji, ki nwọn ki o wá ràn wọn lọwọ. Nwọn si wá, nwọn si kún ọkọ̀ mejeji, bẹ̃ni nwọn bẹ̀rẹ si irì. 8 Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa. 9 Hà si ṣe e, ati gbogbo awọn ti mbẹ pẹlu rẹ̀, fun akopọ̀ ẹja ti nwọn kó: 10 Bẹ̃ ni Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede, ti nṣe olupẹja pọ pẹlu Simoni. Jesu si wi fun Simoni pe, Má bẹ̀ru; lati isisiyi lọ iwọ o ma mú enia. 11 Nigbati nwọn si ti mu ọkọ̀ wọn de ilẹ, nwọn fi gbogbo rẹ̀ silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin lọ.

Jesu Wo Adẹ́tẹ̀ Sàn

12 O si ṣe, nigbati o wọ̀ ilu kan, kiyesi i, ọkunrin kan ti ẹ̀tẹ bò: nigbati o ri Jesu, o wolẹ, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. 13 O si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi kàn a, o ni, Mo fẹ: iwọ di mimọ́. Lọgan ẹ̀tẹ si fi i silẹ lọ. 14 O si kílọ fun u pe, ki o máṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o si fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ́ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹrí si wọn. 15 Ṣugbọn si iwaju li okikí rẹ̀ nkàn kalẹ: ọ̀pọ ijọ enia si jumọ pade lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara lọdọ rẹ̀ kuro lọwọ ailera wọn. 16 O si yẹra si ijù, o si gbadura.

Jesu Wo Ọkunrin Arọ Kan Sàn

17 O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada. 18 Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀. 19 Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu. 20 Nigbati o si ri igbagbọ́ wọn, o wi fun u pe, Ọkunrin yi, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. 21 Awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si igberò, wipe, Tali eleyi ti nsọ ọrọ-odi? Tali o le dari ẹ̀ṣẹ jìni bikoṣe Ọlọrun nikanṣoṣo? 22 Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin? 23 Ewo li o ya jù, lati wipe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide ki iwọ ki o si mã rìn? 24 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si lọ si ile rẹ. 25 O si dide lọgan niwaju wọn, o gbé ohun ti o dubulẹ le, o si lọ si ile rẹ̀, o nyìn Ọlọrun logo. 26 Ẹnu si yà gbogbo wọn, nwọn si nyìn Ọlọrun logo, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwipe, Awa ri ohun abàmi loni.

Jesu Pe Lefi

27 Lẹhin nkan wọnyi o jade lọ, o si ri agbowode kan ti a npè ni Lefi, o joko ni bode: o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. 28 O si fi gbogbo nkan silẹ, o dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin. 29 Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko. 30 Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu. 31 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn dá kò wá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da. 32 Emi kò wá ipè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Gbígbà

33 Nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu fi ngbàwẹ nigbakugba, ti nwọn a si ma gbadura, gẹgẹ bẹ̃ si ni awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi; ṣugbọn awọn tirẹ njẹ, nwọn nmu? 34 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? 35 Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o si gbàwẹ ni ijọ wọnni. 36 O si pa owe kan fun wọn pẹlu pe, Kò si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbo ẹ̀wu; bikoṣepe titun fà a ya, ati pẹlu idãsà titun kò si ba ogbologbo aṣọ rẹ. 37 Kò si si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bikoṣepe ọti-waini titun bẹ́ ìgo na, a si danù, ìgo a si bajẹ. 38 Ṣugbọn ọti-waini titun li a ifi sinu igo titun; awọn mejeji a si ṣe dede. 39 Kò si si ẹniti imu ìsà ọti-waini tan, ti o si fẹ titun lojukanna: nitoriti o ni, ìsà san jù.

Luku 6

Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà Ní Ọjọ́ Ìsinmi

1 O si ṣe li ọjọ isimi keji lẹhin ekini, Jesu kọja larin oko ọkà; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si nya ipẹ́ ọkà, nwọn nfi ọwọ́ ra a jẹ. 2 Awọn kan ninu awọn Farisi si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi? 3 Jesu si da wọn li ohùn, wipe, Ẹnyin kò kawe to bi eyi, bi Dafidi ti ṣe, nigbati ebi npa on tikararẹ̀ ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀; 4 Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si mu akara ifihàn ti o jẹ, ti o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu; ti kò yẹ fun u lati jẹ, bikoṣe fun awọn alufa nikanṣoṣo? 5 O si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi.

Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

6 O si ṣe li ọjọ isimi miran, ti o wọ̀ inu sinagogu lọ, o si nkọ́ni: ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ọtún rọ. 7 Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn. 8 Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro. 9 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Emi o bi nyin lẽre ohunkan; O tọ́ lati mã ṣe ore li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? 10 Nigbati o si wò gbogbo wọn yiká, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si ṣe bẹ̃: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji. 11 Nwọn si kún fun ibinu gbigbona; nwọn si ba ara wọn rò ohun ti awọn iba ṣe si Jesu.

Jesu Yan Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Mejila

12 O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun. 13 Nigbati ilẹ si mọ́, o pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ninu wọn li o si yàn mejila, ti o si sọ ni Aposteli; 14 Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu, 15 Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote, 16 Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

17 O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn; 18 Ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si mu wọn larada. 19 Gbogbo ijọ enia si nfẹ fi ọwọ́ kàn a; nitoriti aṣẹ njade lara rẹ̀, o si mu gbogbo wọn larada.

Ìre ati Ègún

20 Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun. 21 Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin. 22 Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia. 23 Ki ẹnyin ki o yọ̀ ni ijọ na, ki ẹnyin ki o si fò soke fun ayọ̀: sá wò o, ère nyin pọ̀ li ọrun: nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn woli. 24 Ṣugbọn egbé ni fun ẹnyin ọlọrọ̀! nitoriti ẹnyin ti ri irọra nyin na. 25 Egbé ni fun ẹnyin ti o yó! nitoriti ebi yio pa nyin. Egbé ni fun ẹnyin ti nrẹrin nisisiyi! nitoriti ẹnyin o gbàwẹ, ẹnyin o si sọkun. 26 Egbé ni fun nyin, nigbati gbogbo enia ba nsọrọ nyin ni rere! nitori bẹ̃ gẹgẹ li awọn baba wọn ṣe si awọn eke woli.

Ẹ Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Yín

27 Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin. 28 Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin. 29 Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu. 30 Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère. 31 Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu. 32 Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn. 33 Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ. 34 Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada. 35 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu. 36 Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.

Ọ̀rọ̀ Nípa Ṣíṣe Ìdájọ́

37 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin: 38 Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin. 39 O si pa owe kan fun wọn, Afọju le ṣe amọ̀na afọju? awọn mejeji kì yio ṣubu sinu ihò? 40 Ẹniti a nkọ́ ki ijù olukọ́ rẹ̀ lọ: ṣugbọn olukuluku ẹniti o ba pé, yio dabi olukọ́ rẹ̀. 41 Ẽṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? 42 Tabi iwọ o ti ṣe le wi fun arakunrin rẹ pe, Arakunrin, jẹ ki emi ki o yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, nigbati iwọ tikararẹ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? iwọ agabagebe, tètekọ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi kuro ti mbẹ li oju arakunrin rẹ.

Igi ati Èso Rẹ̀

43 Nitori igi rere kì iso eso buburu; bẹ̃ni igi buburu kì iso eso rere. 44 Olukuluku igi li a ifi eso rẹ̀ mọ̀; nitori lori ẹgún oṣuṣu, enia kì iká eso ọpọtọ bẹ̃ni lori ẹgún ọgàn a kì iká eso ajara. 45 Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá; ati enia buburu lati inu iṣura buburu ọkàn rẹ̀ ni imu ohun buburu jade wá: nitori lati ọ̀pọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rẹ̀ isọ.

Ìpìlẹ̀ Meji

46 Ẽsitiṣe ti ẹnyin npè mi li Oluwa, Oluwa, ti ẹnyin kò si ṣe ohun ti mo wi? 47 Ẹnikẹni ti o tọ̀ mi wá, ti o si ngbọ́ ọ̀rọ mi, ti o si nṣe e, emi o fi ẹniti o jọ hàn nyin: 48 O jọ ọkunrin kan ti o kọ́ ile, ti o si walẹ jìn, ti o si fi ipilẹ sọlẹ lori apata: nigbati kíkun omi de, igbi-omi bilù ile na, kò si le mì i: nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori apata. 49 Ṣugbọn ẹniti o gbọ́, ti kò si ṣe, o dabi ọkunrin ti o kọ́ ile si ori ilẹ laini ipilẹ; nigbati igbi-omi bilù u, lọgan o si wó; iwó ile na si pọ̀.

Luku 7

Jesu Wo Ọmọ Ọ̀dọ̀ Balogun Sàn

1 NIGBATI o si pari gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ li eti awọn enia, o wọ̀ Kapernaumu lọ. 2 Ọmọ-ọdọ balogun ọrún kan, ti o ṣọwọn fun u, o ṣaisàn, o nkú lọ. 3 Nigbati o si gburó Jesu, o rán awọn agbagba Ju si i, o mbẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá mu ọmọ-ọdọ on larada. 4 Nigbati nwọn si de ọdọ Jesu, nwọn fi itara bẹ̀ ẹ, wipe, O yẹ li ẹniti on iba ṣe eyi fun: 5 Nitoriti o fẹran orilẹ-ede wa, o si ti kọ́ sinagogu kan fun wa. 6 Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi: 7 Nitorina emi kò si rò pe emi na yẹ lati tọ̀ ọ wá: ṣugbọn sọ ni gbolohùn kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. 8 Nitori emi na pẹlu jẹ ẹniti a fi si abẹ aṣẹ, ti o li ọmọ-ogun li ẹhin mi, mo wi fun ọkan pe, Lọ, a si lọ; ati fun omiran pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. 9 Nigbati Jesu gbọ́ nkan wọnni, ẹnu yà a si i, o si yipada si ijọ enia ti ntọ̀ ọ lẹhin, o wipe, Mo wi fun nyin, emi kò ri irú igbagbọ́ nla bi eyi ninu awọn enia Israeli. 10 Nigbati awọn onṣẹ si pada rè ile, nwọn ba ọmọ-ọdọ na ti nṣaisàn, ara rẹ̀ ti da.

Jesu Jí Ọmọ Opó Kan Dìde Ní Naini

11 O si ṣe ni ijọ keji, o lọ sí ilu kan ti a npè ni Naini; awọn pipọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si mba a lọ ati ọ̀pọ ijọ enia. 12 Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀. 13 Nigbati Oluwa si ri i, ãnu rẹ̀ ṣe e, o si wi fun u pe, Má sọkun mọ́. 14 O si wá, o si fi ọwọ́ tọ́ aga posi na: awọn ti si nrù u duro jẹ. O si wipe, Ọdọmọkunrin, mo wi fun ọ, Dide. 15 Ẹniti o kú na si dide joko, o bẹ̀rẹ si ohùn ifọ̀. O si fà a le iya rẹ̀ lọwọ. 16 Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò. 17 Okikí rẹ̀ si kàn ni gbogbo Judea, ati gbogbo àgbegbe ti o yiká.

Johanu Ranṣẹ Sí Jesu

18 Awọn ọmọ-ẹhin Johanu si fi ninu gbogbo nkan wọnyi hàn fun u. 19 Nigbati Johanu si pè awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o rán wọn sọdọ Jesu, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? 20 Nigbati awọn ọkunrin na si de ọdọ rẹ̀, nwọn ni, Johanu Baptisti rán wa sọdọ rẹ, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? 21 Ni wakati na, o si ṣe dida ara ọpọlọpọ enia ninu aisan, ati arun, ati ẹmi buburu; o si fi iriran fun ọpọlọpọ awọn afọju. 22 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere. 23 Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti ki yio kọsẹ̀ lara mi. 24 Nigbati awọn onṣẹ Johanu pada lọ, o bẹ̀rẹ si isọ fun ijọ enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade rè ijù lọ iwò? ifefe ti afẹfẹ nmì? 25 Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ti a wọ̀ li aṣọ ogo, ti nwọn si njaiye, mbẹ li afin ọba. 26 Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? woli? lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù woli lọ. 27 Eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. 28 Mo wi fun nyin, ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si woli ti o pọ̀ju Johanu Baptisti lọ: ṣugbọn ẹniti o kerejulọ ni ijọba Ọlọrun, o pọ̀ju u lọ. 29 Gbogbo awọn enia ti o gbọ́ ati awọn agbowode, nwọn da Ọlọrun lare, nitori a ti fi baptismu Johanu baptisi wọn. 30 Ṣugbọn awọn Farisi ati awọn amofin kọ ìmọ Ọlọrun fun ara wọn, a kò baptisi wọn lọdọ rẹ̀. 31 Oluwa si wipe, Kili emi iba fi awọn enia iran yi wé? kini nwọn si jọ? 32 Nwọn dabi awọn ọmọ kekere ti o joko ni ibi ọjà, ti nwọn si nkọ si ara wọn, ti nwọn si nwipe, Awa fùn fère fun nyin, ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun. 33 Nitori Johanu Baptisti wá, kò jẹ akara, bẹ̃ni kò si mu ọti-waini; ẹnyin si wipe, O li ẹmi èṣu. 34 Ọmọ-enia de, o njẹ, o si nmu; ẹnyin si wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ! 35 Ṣugbọn a da ọgbọ́n lare lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ gbogbo wá.

Jesu Dárí Ji Obinrin Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kan

36 Farisi kan si rọ̀ ọ ki o wá ba on jẹun. O si wọ̀ ile Farisi na lọ o si joko lati jẹun. 37 Si kiyesi i, obinrin kan wà ni ilu na, ẹniti iṣe ẹlẹṣẹ, nigbati o mọ̀ pe Jesu joko njẹun ni ile Farisi, o mu oruba alabastar ororo ikunra wá, 38 O si duro tì i lẹba ẹsẹ rẹ̀ lẹhin, o nsọkun, o si bẹ̀rẹ si ifi omije wẹ̀ ẹ li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù u nù, o si nfi ẹnu kò o li ẹsẹ, o si nfi ororo kùn wọn. 39 Nigbati Farisi ti o pè e si ri i, o wi ninu ara rẹ̀ pe, ọkunrin yi iba ṣe woli, iba mọ̀ ẹni ati irú ẹniti obinrin yi iṣe ti nfi ọwọ́ kan a: nitori ẹlẹṣẹ ni. 40 Jesu si dahùn wi fun u pe, Simoni, Mo ni ohun kan isọ fun ọ. O si dahùn wipe, Olukọni, mã wi. 41 Onigbese kan wà ti o ni ajigbese meji: ọkan jẹ ẹ ni ẹdẹgbẹta owo idẹ, ekeji si jẹ ẹ ni adọta. 42 Nigbati nwọn kò si ni ti nwọn o san, o darijì awọn mejeji. Wi, ninu awọn mejeji tani yio fẹ ẹ jù? 43 Simoni dahùn o si wipe, mo ṣebi ẹniti o darijì jù ni. O si wi fun u pe, O wi i 're. 44 O si yipada si obinrin na, o wi fun Simoni pe, Iwọ ri obinrin yi? Emi wọ̀ ile rẹ, omi wiwẹ̀ ẹsẹ iwọ kò fifun mi: ṣugbọn on, omije li o fi nrọjo si mi li ẹsẹ, irun ori rẹ̀ li o fi nnù wọn nù. 45 Ifẹnukonu iwọ kò fi fun mi: ṣugbọn on, nigbati mo ti wọ̀ ile, ko dabọ̀ ẹnu ifi kò mi li ẹsẹ. 46 Iwọ kò fi oróro pa mi li ori: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ. 47 Njẹ mo wi fun ọ, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o pọ̀ jì i; nitoriti o ni ifẹ pipọ: ẹniti a si dari diẹ jì, on na li o ni ifẹ diẹ. 48 O si wi fun u pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. 49 Awọn ti o bá a joko njẹun si bẹ̀rẹ si irò ninu ara wọn pe, Tali eyi ti ndari ẹ̀ṣẹ jì-ni pẹlu? 50 O si dahùn wi fun obinrin na pe, Igbagbọ́ rẹ gbà ọ là; mã lọ li alafia.

Luku 8

Àwọn Obinrin Tí Wọn Ń Ran Jesu Lọ́wọ́

1 O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀. 2 Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro, 3 Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.

Òwe Afunrugbin

4 Nigbati ọ̀pọ ijọ enia pejọ pọ̀, lati ilu gbogbo si tọ̀ ọ wá, o fi owe ba wọn sọ̀rọ pe: 5 Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ. 6 Omiran si bọ́ sori apata; bi o si ti hù jade, o gbẹ nitoriti kò ni irinlẹ omi. 7 Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa. 8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

9 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si? 10 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.

Jesu Ṣe Àlàyé Òwe Nípa Afunrugbin

11 Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun. 12 Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là. 13 Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin. 14 Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo. 15 Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.

Fìtílà Tí A Bò Mọ́lẹ̀

16 Kò si ẹnikẹni, nigbati o ba tàn fitilà tan, ti yio fi ohun elò bò o mọlẹ, tabi ti yio gbé e kà abẹ akete; bikoṣe ki o gbé e kà ori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọ̀ ile ki o le ri imọlẹ. 17 Nitori kò si ohun ti o lumọ́, ti a ki yio fi hàn, bẹ̃ni kò si ohun ti o pamọ́, ti a kì yio mọ̀, ti ki yio si yọ si gbangba. 18 Njẹ ki ẹnyin ki o mã kiyesara bi ẹnyin ti ngbọ́: nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a o fifun; ati ẹnikẹni ti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi ti o ṣebi on ni.

Ìyá ati Àwọn Arakunrin Jesu

19 Nigbana ni iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia. 20 Nwọn si wi fun u pe, Iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ri ọ. 21 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Iya mi ati awọn arakunrin mi li awọn wọnyi ti nwọn ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si nṣe e.

Jesu Mú Kí Ìgbì Dákẹ́ Rọ́rọ́

22 O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ. 23 Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu. 24 Nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si da, idakẹ-rọrọ si de. 25 O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.

Jesu Wo Wèrè Ará Geraseni Sàn

26 Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili. 27 Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji. 28 Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró. 29 (Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.) 30 Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? o si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ. 31 Nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe rán wọn lọ sinu ibu. 32 Agbo ẹlẹdẹ pipọ si mbẹ nibẹ̀ ti njẹ li ori òke: nwọn si bẹ̀ ẹ ki o jẹ ki awọn wọ̀ inu wọn lọ. O si jọwọ wọn. 33 Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi. 34 Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na. 35 Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn. 36 Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada. 37 Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin. 38 Njẹ ọkunrin na ti ẹmi èṣu jade kuro lara rẹ̀, o bẹ̀ ẹ ki on ki o le ma bá a gbé: ṣugbọn Jesu rán a lọ, wipe, 39 Pada lọ ile rẹ, ki o si sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọ bi o ti pọ̀ to. O si lọ, o si nròhin já gbogbo ilu na bi Jesu ti ṣe ohun nla fun on to.

Ìtàn Ọmọbinrin Jairu ati Ti Obinrin Tí Ó Fọwọ́ Kan Aṣọ Jesu

40 O si ṣe, nigbati Jesu pada lọ, awọn enia tẹwọgbà a: nitoriti gbogbo nwọn ti nreti rẹ̀. 41 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Jairu, ọkan ninu awọn olori sinagogu, o wá: o si wolẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá si ile on: 42 Nitori o ni ọmọbinrin kanṣoṣo, ọmọ ìwọn ọdún mejila, o nkú lọ. Bi o si ti nlọ awọn enia nhá a li àye. 43 Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá, 44 O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ. 45 Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi? 46 Jesu si wipe, Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi: nitoriti emi mọ̀ pe aṣẹ jade lara mi. 47 Nigbati obinrin na si mọ̀ pe on ko farasin, o warìri, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ fun u li oju awọn enia gbogbo nitori ohun ti o ṣe, ti on fi fi ọwọ́ tọ́ ọ, ati bi a ti mu on larada lojukanna. 48 O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, tújuka: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia. 49 Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, ẹnikan ti ile olori sinagogu wá, o wi fun u pe, Ọmọbinrin rẹ kú; má yọ olukọni lẹnu mọ. 50 Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o da a li ohùn, wipe, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nikan ṣa, a o si mu u larada. 51 Nigbati Jesu si wọ̀ ile, kò jẹ ki ẹnikẹni wọle, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati baba on iya ọmọbinrin na. 52 Gbogbo nwọn si sọkun, nwọn pohùnrere ẹkún rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ má sọkun mọ́; kò kú, sisùn li o sùn. 53 Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú. 54 Nigbati o si sé gbogbo wọn mọ́ ode, o mu u li ọwọ́, o si wipe, Ọmọbinrin, dide. 55 Ẹmí rẹ̀ si pada bọ̀, o si dide lọgan: o ni ki nwọn ki o fun u li onjẹ. 56 Ẹnu si yà awọn õbi rẹ̀: ṣugbọn o kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe wi fun ẹnikan li ohun ti a ṣe.

Luku 9

Iṣẹ́ tí Jesu fi rán àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn mejila

1 O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila jọ, o si fun wọn li agbara on aṣẹ lori awọn ẹmi èṣu gbogbo, ati lati wò arùn sàn. 2 O si rán wọn lọ iwasu ijọba Ọlọrun, ati lati mu awọn olokunrun larada. 3 O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe mu nkan lọ fun àjo nyin, ọpá, tabi àpo tabi akara, tabi owo; bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe ni àwọtẹlẹ meji. 4 Ni ilekile ti ẹnyin ba si wọ̀, nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o gbé, lati ibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ti jade. 5 Iye awọn ti kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn. 6 Nwọn si jade, nwọn nlà iletò lọ, nwọn si nwasu ihinrere, nwọn si nmu enia larada nibi gbogbo.

Hẹrọdu Dààmú

7 Herodu tetrarki si gbọ́ nkan gbogbo ti nṣe lati ọdọ rẹ̀ wá: o si damu, nitoriti awọn ẹlomiran nwipe, Johanu li o jinde kuro ninu okú; 8 Awọn ẹlomiran si wipe Elijah li o farahàn; ati awọn ẹlomiran pe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde. 9 Herodu si wipe, Johanu ni mo ti bẹ́ lori: ṣugbọn tali eyi, ti emi ngbọ́ irú nkan wọnyi si? O si nfẹ lati ri i.

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

10 Nigbati awọn aposteli si pada de, nwọn ròhin ohun gbogbo fun u ti nwọn ti ṣe. O si mu wọn, o si lọ si apakan nibi ijù si ilu ti a npè ni Betsaida. 11 Nigbati ọpọ enia si mọ̀, nwọn tẹle e: o si gbà wọn, o si sọ̀rọ ijọba Ọlọrun fun wọn; awọn ti o fẹ imularada, li o si mu larada. 12 Nigbati ọjọ bẹ̀rẹ si irẹlẹ, awọn mejila wá, nwọn si wi fun u pe, Tú ijọ enia ká, ki nwọn ki o le lọ si iletò ati si ilu yiká, ki nwọn ki o le wọ̀, ati ki nwọn ki o le wá onjẹ: nibi ijù li awa sá gbé wà nihinyi. 13 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Ẹ fi onjẹ fun wọn jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun lọ, pẹlu ẹja meji; bikoṣepe awa lọ irà onjẹ fun gbogbo awọn enia wọnyi. 14 Nitori awọn ọkunrin to ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o mu wọn joko li ẹgbẹ-ẹgbẹ, li aradọta. 15 Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mu gbogbo wọn joko. 16 Nigbana li o mu iṣu akara marun, ati ẹja meji na, nigbati o gbé oju soke, o sure si i, o si bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju awọn enia. 17 Nwọn si jẹ, gbogbo wọn si yó: nwọn ṣà agbọ̀n mejila jọ ninu ajẹkù ti o kù fun wọn.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe

18 O si ṣe, nigbati o kù on nikan, o ngbadura, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wà lọdọ rẹ̀: o si bi wọn pe, Tali awọn enia nfi emi pè? 19 Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti; ṣugbọn ẹlomiran ni, Elijah ni; ati awọn ẹlomiran wipe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde. 20 O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi emi ipè? Peteru si dahùn, wipe, Kristi ti Ọlọrun.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

21 O si kìlọ fun wọn, o si paṣẹ fun wọn, pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun na fun ẹnikan. 22 O si wipe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati lati ọdọ awọn olori alufa, ati lati ọdọ awọn akọwe wá, a o si pa a, ni ijọ kẹta a o si ji i dide. 23 O si wi fun gbogbo wọn pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati mã tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀ ni ijọ gbogbo, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. 24 Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on na ni yio si gbà a là. 25 Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ara rẹ̀ nù, tabi ki o fi ara rẹ̀ ṣòfò. 26 Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, oju rẹ̀ li Ọmọ-enia yio si tì, nigbati o ba de inu ogo tirẹ̀, ati ti baba rẹ̀, ati ti awọn angẹli mimọ́. 27 Ṣugbọn emi wi fun nyin nitõtọ, ẹlomiran duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri ijọba Ọlọrun.

Jesu Paradà Lórí Òkè

28 O si ṣe bi iwọn ijọ kẹjọ lẹhin ọ̀rọ wọnyi, o mu Peteru, ati Johanu, ati Jakọbu, o gùn ori òke lọ lati gbadura. 29 Bi o si ti ngbadura, àwọ oju rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ si fun lawu, o njo fòfo. 30 Si kiyesi i, awọn ọkunrin meji, ti iṣe Mose on Elijah, nwọn mba a sọ̀rọ: 31 Ti nwọn fi ara hàn ninu ogo, nwọn si nsọ̀rọ ikú rẹ̀, ti on ó ṣe pari ni Jerusalemu. 32 Ṣugbọn oju Peteru ati ti awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wuwo fun õrun. Nigbati nwọn si tají, nwọn ri ogo rẹ̀, ati ti awọn ọkunrin mejeji ti o ba a duro. 33 O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi. 34 Bi o ti nsọ bayi, ikũkũ kan wá, o ṣiji bò wọn: ẹ̀ru si ba wọn nigbati nwọn nwọ̀ inu ikuku lọ. 35 Ohùn kan si ti inu ikũkũ wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. 36 Nigbati ohùn na si dakẹ, Jesu nikanṣoṣo li a ri. Nwọn si pa a mọ́, nwọn kò si sọ ohunkohun ti nwọn ri fun ẹnikẹni ni ijọ wọnni.

Jesu Wo Ọmọ tí Ó ní Wárápá Sàn

37 O si ṣe, ni ijọ keji, nigbati nwọn sọkalẹ lati ori òke wá, ọ̀pọ awọn enia wá ipade rẹ̀. 38 Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni. 39 Si kiyesi i, ẹmi èṣu a ma mu u, a si ma kigbe lojijì; a si ma nà a tàntàn titi yio fi yọ ifofó li ẹnu, a ma pa a lara, a tilẹ fẹrẹ má fi i silẹ lọ. 40 Mo si bẹ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati lé e jade; nwọn kò si le ṣe e. 41 Jesu si dahùn, wipe, Iran alaigbagbọ́ ati arekereke, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti ṣe sũru fun nyin pẹ to? Fà ọmọ rẹ wá nihinyi. 42 Bi o si ti mbọ̀, ẹmi èṣu na gbé e ṣanlẹ, o si nà a tantan. Jesu si ba ẹmi aimọ́ na wi, o si mu ọmọ na larada, o si fà a le baba rẹ̀ lọwọ. 43 Ẹnu si yà gbogbo wọn si iṣẹ ọlánla Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati hà si nṣe gbogbo wọn si ohun gbogbo ti Jesu ṣe, o wi fun awon ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe,

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú Rẹ̀

44 Ẹ jẹ ki ọrọ wọnyi ki o rì si nyin li etí: nitori a o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ. 45 Ṣugbọn ọ̀rọ na ko yé wọn, o si ṣú wọn li oju, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ ọ: ẹ̀ru si mba wọn lati bère idi ọ̀rọ na.

Ta Ni Ẹni Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ?

46 Iyan kan si dide lãrin wọn, niti ẹniti yio ṣe olori ninu wọn. 47 Nigbati Jesu si mọ̀ ìro ọkàn wọn, o mu ọmọde kan, o gbé e joko lọdọ rẹ̀, 48 O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọmọde yi nitori orukọ mi, o gbà mi: ati ẹnikẹni ti o ba gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi: nitori ẹniti o ba kere ju ninu gbogbo nyin, on na ni yio pọ̀.

Ẹni Tí Kò Bá Lòdì sí Yín, Tiyín ni

49 Johanu si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, awa ri ẹnikan o nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade; awa si da a lẹkun, nitoriti kò ba wa tọ̀ ọ lẹhin. 50 Jesu si wi fun u pe, Máṣe da a lẹkun mọ́: nitori ẹniti kò ba lodi si wa, o wà fun wa.

Àwọn Ará Abúlé Samaria Kan Kọ Jesu

51 O si ṣe, nigbati ọjọ atigbà soke rẹ̀ pé, o gbé oju le gangan lati lọ si Jerusalemu. 52 O si rán awọn onṣẹ lọ si iwaju rẹ̀: nigbati nwọn si lọ nwọn wọ̀ iletò kan ti iṣe ti ara Samaria lọ ipèse silẹ dè e. 53 Nwọn kò si gbà a, nitoriti oju rẹ̀ dabi ẹnipe o nlọ si Jerusalemu. 54 Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ Jakọbu on Johanu si ri i, nwọn ni, Oluwa, iwọ ko jẹ ki awa ki o pè iná lati ọrun wá, ki a sun wọn lúlu, bi Elijah ti ṣe? 55 Ṣugbọn Jesu yipada, o si ba wọn wi, o ni, Ẹnyin kò mọ̀ irú ẹmí ti mbẹ ninu nyin. 56 Nitori Ọmọ-enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là. Nwọn si lọ si iletò miran.

Àwọn Tí Ó Fẹ́ Tẹ̀lé Jesu

57 O si ṣe, bi nwọn ti nlọ li ọ̀na, ọkunrin kan wi fun u pe, Oluwa, Emi nfẹ lati ma tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ ba nlọ. 58 Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio fi ori rẹ̀ le. 59 O si wi fun ẹlomiran pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn o wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinku baba mi na. 60 Jesu si wi fun u pe, Je ki awọn okú ki o mã sinkú ara wọn: ṣugbọn iwọ lọ ki o si mã wãsu ijọba Ọlọrun. 61 Ẹlomiran si wi fun u pe, Oluwa, emi nfẹ lati mã tọ̀ ọ lẹhin; ṣugbọn jẹ ki emi ki o pada lọ idagbere fun awọn ara ile mi. 62 Jesu si wi fun u pe, Kò si ẹni, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ le ohun-elo itulẹ, ti o si wò ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun.

Luku 10

Àwọn tí ó fẹ́ tẹ̀lé Jesu

1 LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de. 2 O si wi fun wọn pe, Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ̀ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀. 3 Ẹ mu ọ̀na nyin pọ̀n: sa wò o, emi rán nyin lọ bi ọdọ-agutan sãrin ikõkò. 4 Ẹ máṣe mu asuwọn, ẹ máṣe mu apò, tabi bàta: ẹ má si ṣe kí ẹnikẹni li ọ̀na. 5 Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi. 6 Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin. 7 Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile. 8 Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin: 9 Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin. 10 Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe, 11 Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin. 12 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ni ijọ na, jù fun ilu na lọ.

Jesu Dárò Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada

13 Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru. 14 Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ. 15 Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku. 16 Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.

Àwọn Mejilelaadọrin Pada Dé

17 Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ. 18 O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá. 19 Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara. 20 Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.

Jesu Láyọ̀

21 Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ. 22 Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ ẹniti Ọmọ iṣe, bikoṣe Baba; ati ẹniti Baba iṣe, bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti o ba si wù Ọmọ lati fi i hàn fun. 23 O si yipada si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li apakan, o ni, Ibukún ni fun ojú ti nri ohun ti ẹnyin nri: 24 Nitori mo wi fun nyin, Woli ati ọba pipọ li o nfẹ lati ri ohun ti ẹnyin nri, nwọn kò si ri wọn, ati lati gbọ ohun ti ẹnyin ngbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn,

Aláàánú Ará Samaria

25 Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun? 26 O si bi i pe, Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a? 27 O si dahùn wipe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ. 28 O si wi fun u pe, Iwọ dahùn rere: ṣe eyi, iwọ o si yè. 29 Ṣugbọn o nfẹ lati dá ara rẹ̀ lare, o wi fun Jesu pe, Tani ha si li ẹnikeji mi? 30 Jesu si dahùn o wipe, ọkunrin kan nti Jerusalemu sọkalẹ lọ si Jeriko, o si bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà, ti nwọn gbà a li aṣọ, nwọn ṣá a lọgbẹ, nwọn si fi i silẹ lọ li aipa li apatan. 31 Ni alabapade, alufa kan si nsọkalẹ lọ lọna na: nigbati o si ri i, o kọja lọ niha keji. 32 Bẹ̃na si ni ọmọ Lefi kan pẹlu, nigbati o de ibẹ̀, ti o si ri i, o kọja lọ niha keji. 33 Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrè àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e, 34 O si tọ̀ ọ lọ, o si dì i lọgbẹ, o da oróro on ọti-waini si i, o si gbé e le ori ẹranko ti on tikalarẹ̀, o si mu u wá si ile-èro, o si nṣe itọju rẹ̀. 35 Nigbati o si lọ ni ijọ keji, o fi owo idẹ meji fun olori ile-ero, o si wi fun u pe, Mã tọju rẹ̀; ohunkohun ti iwọ ba si ná kun u, nigbati mo ba pada de, emi ó san a fun ọ. 36 Ninu awọn mẹtẹta wọnyi, tani iwọ rò pe iṣe ẹnikeji ẹniti o bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà? 37 O si dahùn wipe, Ẹniti o ṣãnu fun u ni. Jesu si wi fun u pe, Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.

Jesu Bẹ Mata ati Maria Wò

38 O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, o wọ̀ iletò kan: obinrin kan ti a npè ni Marta si gbà a si ile rẹ̀. 39 O si ni arabinrin kan ti a npè ni Maria, ti o si joko lẹba ẹsẹ Jesu, ti o ngbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. 40 Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ. 41 Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ: 42 Ṣugbọn ohun kan li a kò le ṣe alaini. Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kò le gbà lọwọ rẹ̀.

Luku 11

Adura Oluwa

1 O si ṣe, bi o ti ngbadura ni ibi kan, bi o ti dakẹ, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, kọ́ wa bi ãti igbadura, bi Johanu si ti kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 2 O si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ mã wipe, Baba wa ti mbẹ li ọrun, Ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹni li aiye. 3 Fun wa li onjẹ ojọ wa li ojojumọ́. 4 Ki o si dari ẹ̀ṣẹ wa jì wa; nitori awa tikarawa pẹlu a ma darijì olukuluku ẹniti o jẹ wa ni gbese. Má si fà wa sinu idẹwò; ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. 5 O si wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti yio ni ọrẹ́ kan, ti yio si tọ̀ ọ lọ larin ọganjọ, ti yio si wi fun u pe, Ọrẹ́, win mi ni ìṣu akara mẹta: 6 Nitori ọrẹ́ mi kan ti àjo bọ sọdọ mi, emi kò si ni nkan ti emi o gbé kalẹ niwaju rẹ̀; 7 Ti on o si gbé inu ile dahùn wi fun u pe, Má yọ mi lẹnu: a ti sé ilẹkun na, awọn ọmọ mi si mbẹ lori ẹní pẹlu mi; emi ko le dide fifun ọ? 8 Mo wi fun nyin, bi on kò tilẹ fẹ dide ki o fifun u, nitoriti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ̀ yio dide, yio si fun u pọ̀ to bi o ti nfẹ. 9 Emi si wi fun nyin, Ẹ bère, a o si fifun nyin; ẹ wá kiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin. 10 Nitori ẹnikẹni ti o ba bère, o ri gbà; ẹniti o si nwá kiri o ri; ati ẹniti o kànkun li a o ṣí i silẹ fun. 11 Tani iṣe baba ninu nyin ti ọmọ rẹ̀ yio bère akara lọdọ rẹ̀, ti o jẹ fun u li okuta? tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò dipo ẹja? 12 Tabi bi o si bère ẹyin, ti o jẹ fun u li akẽkẽ? 13 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ̀ bi ãti ifi ẹ̀bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ fun awọn ti o mbère lọdọ rẹ̀?

Jesu ati Beelsebulu

14 O si nlé ẹmi èṣu kan jade, ti o si yadi. O si ṣe, nigbati ẹmi èṣu na jade, odi sọrọ; ẹnu si yà ijọ enia. 15 Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn wipe, Nipa Beelsebubu olori awọn ẹmi èṣu li o fi nlé awọn ẹmi èṣu jade. 16 Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá. 17 Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó. 18 Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade. 19 Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin. 20 Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin. 21 Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia: 22 Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀. 23 Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká. 24 Nigbati ẹmi aimọ́ ba jade kuro lara enia, ama rìn kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati ko ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá. 25 Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ́. 26 Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ.

Ẹni Tí Ó ní Ibukun Tòótọ́

27 O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu. 28 Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́.

Àwọn Kan Bèèrè Àmì Lọ́wọ́ Jesu

29 Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ si iwipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli. 30 Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi. 31 Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi. 32 Awọn ara Ninefe yio dide li ọjọ idajọ pẹlu iran yi, nwọn o si da a lẹbi: nitoriti nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Jona lọ mbẹ nihinyi.

Ìmọ́lẹ̀ Ara

33 Kò si ẹnikan, nigbati o ba tan fitila tán, ti igbé e si ìkọkọ, tabi sabẹ oṣuwọn, bikoṣe sori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọle ba le mã ri imọlẹ. 34 Oju ni imọlẹ ara: bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ a mọlẹ; ṣugbọn bi oju rẹ ba buru, ara rẹ pẹlu a kun fun òkunkun. 35 Nitorina kiyesi i, ki imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ki o máṣe di òkunkun. 36 Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ.

Jesu Bá Àwọn Farisi ati Àwọn Akọ̀wé Wí

37 Bi o si ti nwi, Farisi kan bẹ̀ ẹ ki o ba on jẹun: o si wọle, o joko lati jẹun. 38 Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun. 39 Oluwa si wi fun u pe, Ẹnyin Farisi a ma fọ̀ ode ago ati awopọkọ́; ṣugbọn inu nyin kún fun irẹjẹ iwa-buburu. 40 Ẹnyin alaimoye, ẹniti o ṣe eyi ti mbẹ lode, on kọ́ ha ṣe eyi ti mbẹ ninu pẹlu? 41 Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin. 42 Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin a ma san idamẹwa minti, ati rue, ati gbogbo ewebẹ̀, ṣugbọn ẹnyin gbojufò idajọ ati ifẹ Ọlọrun: wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe. 43 Egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin fẹ ipò-ọlá ninu sinagogu, ati ikí-ni li ọjà. 44 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe, ati ẹnyin Farisi, agabagebe! nitoriti ẹnyin dabi isa okú ti kò hàn, awọn enia ti o si nrìn lori wọn kò mọ̀. 45 Nigbana li ọkan ninu awọn amofin dahùn, o si wi fun u pe, Olukọni, li eyi ti iwọ nwi nì iwọ ngàn awa pẹlu. 46 O si wipe, Egbé ni fun ẹnyin amofin pẹlu! nitoriti ẹnyin di ẹrù ti o wuwo lati rù le enia lori, bẹ̃ni ẹnyin tikara nyin kò jẹ fi ika nyin kan kàn ẹrù na. 47 Egbé ni fun nyin! nitoriti ẹnyin kọ́le oju-õrì awọn woli, awọn baba nyin li o si ti pa wọn. 48 Njẹ ẹnyin njẹ ẹlẹri, ẹ si ni inudidun si iṣe awọn baba nyin: nitori nwọn pa wọn, ẹnyin si kọ́le oju-õrì wọn. 49 Nitori eyi li ọgbọ́n Ọlọrun si ṣe wipe, emi ó rán awọn woli ati awọn aposteli si wọn, ninu wọn ni nwọn o si pa, ti nwọn o si ṣe inunibini si: 50 Ki a le bère ẹ̀jẹ awọn woli gbogbo, ti a ti ta silẹ lati igba ipilẹṣẹ aiye wá, lọdọ iran yi; 51 Lati ẹ̀jẹ Abeli wá, titi o si fi de ẹ̀jẹ Sakariah, ti o ṣegbé lãrin pẹpẹ on tẹmpili: lõtọ ni mo wi fun nyin, A o bère rẹ̀ lọdọ iran yi. 52 Egbé ni fun nyin, ẹnyin amofin! nitoriti ẹnyin gbà ọmọ-ṣika ìmọ: ẹnyin tikaranyin kò wọle, awọn ti si nwọle, li ẹnyin kọ̀ fun. 53 Bi o ti nwi nkan wọnyi fun wọn, awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si ibinu si i gidigidi, nwọn si nyọ ọ lẹnu lati wi nkan pipọ: 54 Nwọn nṣọ ọ, nwọn nwá ọ̀na ati ri nkan gbámu li ẹnu rẹ̀, ki nwọn ki o le fi i sùn.

Luku 12

Jesu Ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àgàbàgebè

1 O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe. 2 Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀. 3 Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.

Ẹni Tí Ó Yẹ Láti Bẹ̀rù

4 Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́. 5 Ṣugbọn emi o si sọ ẹniti ẹnyin o bẹ̀ru fun nyin: Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pani tan, lati wọ́ni lọ si ọrun apadi; lõtọ ni mo wi fun nyin, On ni ki ẹ bẹru. 6 Ologoṣẹ marun ki a ntà li owo idẹ wẹ́wẹ meji? a kò si gbagbé ọkan ninu wọn niwaju Ọlọrun? 7 Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ki ẹ máṣe bẹ̀ru: ẹnyin ni iye lori jù ologoṣẹ pipọ lọ.

Jíjẹ́wọ́ Jesu Níwájú Eniyan

8 Mo si wi fun nyin pẹlu, Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, Ọmọ-ẹnia yio si jẹwọ rẹ̀ niwaju awọn angẹli Ọlọrun: 9 Ṣugbọn ẹniti o ba sẹ́ mi niwaju enia, a o sẹ́ ẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun. 10 Ati ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ-òdi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a kì yio dari rẹ̀ jì i. 11 Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi: 12 Nitori Ẹmí Mimọ́ yio kọ́ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi.

Òwe Nípa Aṣiwèrè Ọlọ́rọ̀

13 Ọkan ninu awujọ si wi fun u pe, Olukọni, sọ fun arakunrin mi ki o pín mi li ogún. 14 O si wi fun u pe, ọkunrin yi, tali o fi mi jẹ onidajọ tabi olùpín-ogún wá fun nyin? 15 O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni. 16 O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ: 17 O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si? 18 O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si. 19 Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀. 20 Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ? 21 Bẹ̃ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti ko si li ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.

Ẹ̀kọ́ Nípa Ṣíṣe Àníyàn

22 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora. 23 Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ. 24 Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? 25 Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? 26 Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? 27 Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. 28 Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? 29 Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. 30 Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. 31 Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin.

Ìṣúra Ní Ọ̀run

32 Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin. 33 Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ. 34 Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.

Àwọn Ọmọ-Ọ̀dọ̀ Tí Ó Ń Ṣọ́nà

35 Ẹ di amure nyin, ki fitila nyin ki o si mã jo: 36 Ki ẹnyin tikara nyin ki o dabi ẹniti nreti oluwa wọn, nigbati on o pada ti ibi iyawo de; pe, nigbati o ba de, ti o si kànkun, ki nwọn ki o le ṣí i silẹ fun u lọgan. 37 Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yio ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rẹ̀ li amure, yio si mu wọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn. 38 Bi o ba si de nigba iṣọ keji, tabi ti o si de nigba iṣọ kẹta, ti o si ba wọn bẹ̃, ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni. 39 Ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati ti olè yio wá, on iba ma ṣọna, kì ba ti jẹ ki a lu ile on já. 40 Nitorina ki ẹnyin ki o mura pẹlu: Nitori Ọmọ-enia mbọ̀ ni wakati ti ẹnyin kò daba.

Ẹrú Olódodo ati Ẹrú Alaiṣododo

41 Peteru si wipe, Oluwa, iwọ pa owe yi fun wa, tabi fun gbogbo enia? 42 Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò? 43 Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃. 44 Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni. 45 Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara; 46 Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́. 47 Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ. 48 Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i.

Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

49 Iná li emi wá lati fọ̀n si aiye; kili emi si nfẹ bi a ba ti da a ná? 50 Ṣugbọn emi ni baptismu kan ti a o fi baptisi mi; ara ti nni mi to titi yio fi pari! 51 Ẹnyin ṣebi alafia li emi wá fi si aiye? mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ; ki a sá kuku pe iyapa: 52 Nitori lati isisiyi lọ, enia marun yio wà ni ile kanna ti a o yà ni ipa, mẹta si meji, ati meji si mẹta. 53 A o yà baba ni ipa si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọkunrin si baba; iya si ọmọbinrin rẹ̀, ati ọmọbinrin si iya rẹ̀; iyakọ si iyawo rẹ̀, ati iyawo si iyako rẹ̀.

Àmì Àkókò

54 O si wi fun ijọ enia pẹlu pe, Nigbati ẹnyin ba ri awọsanma ti o ṣú ni ìha ìwọ-õrùn, ọgan ẹnyin a ni, Ọwara òjo mbọ̀; a si ri bẹ̃. 55 Nigbati afẹfẹ gusù ba nfẹ, ẹnyin a ni, Õru yio mu; a si ṣẹ. 56 Ẹnyin agabagebe, ẹnyin le moye oju ọrun ati ti aiye; ẽhatiṣe ti ẹnyin kò le mọ̀ akokò yi?

Ẹ Bá Ọ̀tá Yín Rẹ́

57 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin tikara nyin ko fi rò ohun ti o tọ́? 58 Nigbati iwọ ba mbá ọtá rẹ lọ sọdọ olóri, mura li ọ̀na ki a le gbà ọ lọwọ rẹ̀; ki o máṣe fi ọ le onidajọ lọwọ, ki onidajọ máṣe fi ọ le ẹṣọ lọwọ, on a si tì ọ sinu tubu. 59 Ki emi ki o wi fun ọ, iwọ ki yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.

Luku 13

Ẹ Ronupiwada, Bí Bẹ́ẹ̀ Kọ̀ Ẹ Óo Ṣègbé

1 AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn. 2 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni? 3 Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. 4 Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ? 5 Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.

Ẹ̀kọ́ Nípa Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Kò Léso

6 O si pa owe yi fun wọn pe; ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan. 7 O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu? 8 O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i: 9 Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulẹ̀. 10 O si nkọ́ni ninu sinagogu kan li ọjọ isimi. 11 Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe. 12 Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ. 13 O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo. 14 Olori sinagogu si kun fun irunu, nitoriti Jesu muni larada li ọjọ isimi, o si wi fun ijọ enia pe, Ijọ mẹfa ni mbẹ ti a fi iṣiṣẹ: ninu wọn ni ki ẹnyin ki o wá ki a ṣe dida ara nyin, ki o máṣẹ li ọjọ isimi. 15 Nigbana li Oluwa dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnyin agabagebe, olukuluku nyin ki itú malu tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ kuro nibuso, ki si ifà a lọ imu omi li ọjọ isimi? 16 Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá? 17 Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá.

Àwọn Òwe Nípa Wóró Mustardi ati Nípa Ìwúkàrà

18 O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé? 19 O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀. 20 O si tún wipe, Kili emi iba fi ijọba Ọlọrun wé? 21 O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu.

Ẹnu Ìlẹ̀kùn Tí Ó Há

22 O si nlà arin ilu ati iletò lọ, o nkọ́ni, o si nrìn lọ si iha Jerusalemu. 23 Ẹnikan si bi i pe, Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà? O si wi fun wọn pe, 24 Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle. 25 Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá: 26 Nigbana li ẹnyin o bẹ̀rẹ si iwipe, Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọ́ni ni igboro ilu wa. 27 On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ. 28 Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode. 29 Nwọn o si ti ìla-õrùn, ati ìwọ-õrùn wá, ati lati ariwa, ati gusù wá, nwọn o si joko ni ijọba Ọlọrun. 30 Si wo o, awọn ẹni-ẹ̀hin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ, ti yio di ẹni-ẹ̀hin.

Jesu Dárò Jerusalẹmu

31 Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ. 32 O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe. 33 Ṣugbọn emi kò jẹ má rìn loni, ati lọla, ati li ọtunla: kò le jẹ bẹ̃ pe woli ṣegbé lẹhin odi Jerusalemu. 34 Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! 35 Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.

Luku 14

Jesu Wo Ọkunrin Tí Ó Ní Àsunkún

1 O si ṣe, nigbati o wọ̀ ile ọkan ninu awọn olori Farisi lọ li ọjọ isimi lati jẹun, nwọn si nṣọ ọ. 2 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti o li asunkun mbẹ niwaju rẹ̀. 3 Jesu si dahùn o wi fun awọn amofin ati awọn Farisi pe, O ha tọ́ lati mu-ni larada li ọjọ isimi, tabi kò tọ? 4 Nwọn si dakẹ. O si mu u, o mu u larada, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ; 5 O si dahùn o wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti kẹtẹkẹtẹ tabi malu rẹ̀ yio bọ sinu ihò, ti kì yio si fà a soke lojukanna li ọjọ isimi? 6 Nwọn kò si le da a li ohùn mọ́ si nkan wọnyi.

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìrẹ̀lẹ̀

7 O si pa owe kan fun awọn ti a pè wá jẹun, nigbati o wò bi nwọn ti nyàn ipò ọlá; o si wi fun wọn pe, 8 Nigbati ẹnikan ba pè ọ wá si ibi iyawo, máṣe joko ni ipò ọlá; ki o ma ba jẹ pe, a pè ẹniti o li ọlá jù ọ lọ. 9 Nigbati ẹniti o pè ọ ati on ba de, a si wi fun ọ pe, Fun ọkunrin yi li àye; iwọ a si wa fi itiju mu ipò ẹhin. 10 Ṣugbọn nigbati a ba pè ọ, lọ ki o si joko ni ipò ẹhin; nigbati ẹniti o pè ọ ba de, ki o le wi fun ọ pe, Ọrẹ́, bọ́ soke: nigbana ni iwọ o ni iyin li oju awọn ti o ba ọ joko ti onjẹ. 11 Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, li a o si gbéga. 12 Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ. 13 Ṣugbọn nigbati iwọ ba se àse, pè awọn talakà, awọn alabùkù arùn, awọn amukun, ati awọn afọju: 14 Iwọ o si jẹ alabukun fun; nitori nwọn kò ni ohun ti nwọn o fi san a fun ọ: ṣugbọn a o san a fun ọ li ajinde awọn olõtọ.

Òwe Nípa Àsè Ńlá

15 Nigbati ọkan ninu awọn ti o ba a joko tì onjẹ gbọ́ nkan wọnyi, o wi fun u pe, Ibukun ni fun ẹniti yio jẹun ni ijọba Ọlọrun. 16 Ṣugbọn o wi fun u pe, ọkunrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ: 17 O si rán ọmọ-odọ rẹ̀ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọn ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan. 18 Gbogbo wọn so bẹ̀rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi. Ekini wi fun u pe, Mo rà ilẹ kan, emi kò si le ṣe ki ng má lọ iwò o: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi. 19 Ekeji si wipe, Mo rà ajaga malu marun, mo si nlọ idán wọn wò: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi. 20 Ẹkẹta si wipe, Mo gbeyawo, nitorina li emi kò fi le wá. 21 Ọmọ-ọdọ na si pada de, o sọ nkan wọnyi fun oluwa rẹ̀. Nigbana ni bãle ile binu, o wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Jade lọ si igboro, ati si abuja ọ̀na, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amukun, ati awọn afọju wá si ihinyi. 22 Ọmọ-ọdọ na si wipe, Oluwa, a ti ṣe bi o ti paṣẹ, àye si mbẹ sibẹ. 23 Oluwa na si wi fun ọmọ-ọdọ na pe, Jade lọ si opópo, ati si ọ̀na ọgbà, ki o si rọ̀ wọn lati wọle wá, ki ile mi le kún. 24 Nitori mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pè, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi.

Ohun Tí Eniyan Gbọdọ̀ Ṣe Kí Ó Tó Lè Jẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn

25 Awọn ọpọ ijọ enia mba a lọ: o si yipada, o si wi fun wọn pe, 26 Bi ẹnikan ba tọ̀ mi wá, ti ko si korira baba rẹ̀, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabinrin, ani ati ẹmí ara rẹ̀ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi. 27 Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ̀, ki o si ma tọ̀ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi. 28 Nitori tani ninu nyin ti npete ati kọ́ ile-iṣọ, ti kì yio kọ́ joko ki o ṣiro iye owo rẹ̀, bi on ni to ti yio fi pari rẹ̀. 29 Ki o ma ba jẹ pe nigbati o ba fi ipilẹ ile sọlẹ tan, ti kò le pari rẹ̀ mọ́, gbogbo awọn ti o ri i a bẹ̀rẹ si ifi i ṣe ẹlẹyà, 30 Wipe, ọkunrin yi bẹ̀rẹ si ile ikọ́, kò si le pari rẹ̀. 31 Tabi ọba wo ni nlọ ibá ọba miran jà, ti kì yio kọ́ joko, ki o si gbèro bi yio le fi ẹgbarun padegun ẹniti nmu ẹgbawa bọ̀ wá kò on loju? 32 Bi bẹ̃kọ nigbati onitọhun si wà li òkere, on a ran ikọ si i, a si bere ipinhùn alafia. 33 Gẹgẹ bẹ̃ni, ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin, ti kò ba kò ohun gbogbo ti o ni silẹ, kọ̀ le ṣe ọmọ-ẹhin mi.

Iyọ̀ Tí Ó Di Òbu

34 Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kili a o fi mu u dùn? 35 Kò yẹ fun ilẹ, bẽni kò yẹ fun àtan; bikoṣepe ki a kó o danù. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́ ki o gbọ́.

Luku 15

Òwe Nípa Agutan tí Ó Sọnù

1 GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. 2 Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun. 3 O si pa owe yi fun wọn, wipe. 4 Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i? 5 Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ. 6 Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù. 7 Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada.

Òwe Nípa Fàdákà tí Ó Sọnù

8 Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i? 9 Nigbati o si ri i, o pè awọn ọrẹ́ ati awọn aladugbo rẹ̀ jọ, o wipe, Ẹ ba mi yọ̀; nitori mo ri fadakà ti mo ti sọnù. 10 Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada. 11 O si wipe, ọkunrin kan li ọmọkunrin meji: 12 Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn. 13 Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna. 14 Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini. 15 O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ. 16 Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u. 17 Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin. 18 Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ; 19 Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ. 20 O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. 21 Ọmọ na si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi kò yẹ li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́. 22 Ṣugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mu ãyo aṣọ wá kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ; ẹ si fi oruka bọ̀ ọ lọwọ, ati bàta si ẹsẹ rẹ̀: 23 Ẹ si mu ẹgbọ̀rọ malu abọpa wá, ki ẹ si pa a; ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya: 24 Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i. Nwọn si bẹ̀re si iṣe ariya. 25 Ṣugbọn ọmọ rẹ̀ eyi ẹgbọn ti wà li oko: bi o si ti mbọ̀, ti o sunmọ eti ile, o gbọ́ orin on ijó. 26 O si pè ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ wọn, o bère, kili ã mọ̀ nkan wọnyi si? 27 O si wi fun u pe, Aburo rẹ de; baba rẹ si pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa, nitoriti o ri i pada li alafia ati ni ilera. 28 O si binu, o si kọ̀ lati wọle; baba rẹ̀ si jade, o si wá iṣipẹ fun u. 29 O si dahùn o wi fun baba rẹ̀ pe, Wo o, lati ọdún melo wọnyi li emi ti nsin ọ, emi kò si ru ofin rẹ ri: iwọ kò si ti ifi ọmọ ewurẹ kan fun mi, lati fi ba awọn ọrẹ́ mi ṣe ariya: 30 Ṣugbọn nigbati ọmọ rẹ yi de, ẹniti o fi panṣaga run ọrọ̀ rẹ, iwọ si ti pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa fun u. 31 O si wi fun u pe, Ọmọ, nigbagbogbo ni iwọ mbẹ lọdọ mi, ohun gbogbo ti mo si ni, tìrẹ ni. 32 O yẹ ki a ṣe ariya ki a si yọ̀: nitori aburo rẹ yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i.

Luku 16

Òwe Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n Ẹ̀wẹ́

1 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo. 2 Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́. 3 Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi. 4 Mo mọ̀ eyiti emi o ṣe, nigbati a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki nwọn ki o le gbà mi sinu ile wọn. 5 O si pè awọn ajigbese oluwa rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun ekini pe, Elo ni iwọ jẹ oluwa mi? 6 O si wipe, Ọgọrun oṣuwọn oróro. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, si joko nisisiyi, ki o si kọ adọta. 7 Nigbana li o si bi ẹnikeji pe, Elo ni iwọ jẹ? On si wipe, Ọgọrun oṣuwọn alikama. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, ki o si kọ ọgọrin. 8 Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ. 9 Emi si wi fun nyin, ẹ fi mammoni aiṣõtọ yàn ọrẹ́ fun ara nyin pe, nigbati yio ba yẹ̀, ki nwọn ki o le gbà nyin si ibujoko wọn titi aiye. 10 Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipo pẹlu. 11 Njẹ bi ẹnyin kò ba ti jẹ olõtọ ni mammoni aiṣõtọ, tani yio fi ọrọ̀ tõtọ ṣú nyin? 12 Bi ẹnyin ko ba si ti jẹ olõtọ li ohun ti iṣe ti ẹlomiran, tani yio fun nyin li ohun ti iṣe ti ẹnyin tikara nyin? 13 Kò si iranṣẹ kan ti o le sin oluwa meji: ayaṣebi yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio fi ara mọ́ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin kò le sin Ọlọrun pẹlu mammoni.

Òfin ati Ìjọba Ọlọrun

14 Awọn Farisi, ti nwọn ni ojukokoro si gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, nwọn si yọ-ṣùti si i. 15 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun. 16 Ofin ati awọn woli mbẹ titi di igba Johanu: lati igbana wá li a ti nwasu ijọba Ọlọrun, olukuluku si nfi ipá wọ̀ inu rẹ̀. 17 Ṣugbọn o rọrun fun ọrun on aiye lati kọja lọ, jù ki ṣonṣo kan ti ofin ki o yẹ̀. 18 Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé, ẹniti ọkọ rẹ̀ kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ ati Lasaru

19 Njẹ ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o nwọ̀ aṣọ elesè àluko ati aṣọ àla daradara, a si ma jẹ didùndidun lojojumọ́: 20 Alagbe kan si wà ti a npè ni Lasaru, ti nwọn ima gbé wá kalẹ lẹba ọ̀na ile rẹ̀, o kún fun õju, 21 On a si ma fẹ ki a fi ẹrún ti o ti ori tabili ọlọrọ̀ bọ silẹ bọ́ on: awọn ajá si wá, nwọn si fá a li õju lá. 22 O si ṣe, alagbe kú, a si ti ọwọ́ awọn angẹli gbé e lọ si õkan-àiya Abrahamu: ọlọrọ̀ na si kú pẹlu, a si sin i; 23 Ni ipo-oku li o gbé oju rẹ̀ soke, o mbẹ ninu iṣẹ oró, o si ri Abrahamu li òkere, ati Lasaru li õkan-àiya rẹ̀. 24 O si ke, o wipe, Baba Abrahamu, ṣãnu fun mi, ki o si rán Lasaru, ki o tẹ̀ orika rẹ̀ bọmi, ki o si fi tù mi li ahọn; nitori emi njoró ninu ọwọ́ iná yi. 25 Ṣugbọn Abrahamu wipe, Ọmọ, ranti pe, nigba aiye rẹ, iwọ ti gbà ohun rere tirẹ, ati Lasaru ohun buburu: ṣugbọn nisisiyi ara rọ̀ ọ, iwọ si njoro. 26 Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbe ọgbun nla kan si agbedemeji awa ati ẹnyin, ki awọn ti nfẹ má ba le rekọja lati ìhin lọ sọdọ nyin, ki ẹnikẹni má si le ti ọ̀hun rekọja tọ̀ wa wá. 27 O si wipe, Njẹ mo bẹ̀ ọ, baba, ki iwọ ki o rán a lọ si ile baba mi: 28 Nitori mo ni arakunrin marun; ki o le rò fun wọn ki awọn ki o má ba wá si ibi oró yi pẹlu. 29 Abrahamu si wi fun u pe, Nwọn ni Mose ati awọn woli; ki nwọn ki o gbọ́ ti wọn. 30 O si wipe, Bẹ̃kọ, Abrahamu baba; ṣugbọn bi ẹnikan ba ti inu okú tọ̀ wọn lọ, nwọn ó ronupiwada. 31 O si wi fun u pe, Bi nwọn kò ba gbọ́ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkan pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide.

Luku 17

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ohun Ìkọsẹ̀

1 O SI wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ko le ṣe ki ohun ikọsẹ̀ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ̀ de. 2 Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ̀. 3 Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀

4 Bi o ba si ṣẹ̀ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ̀ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari jì i. 5 Awọn aposteli si wi fun Oluwa pe, Busi igbagbọ́ wa. 6 Oluwa si wipe, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irugbin mustardi, ẹnyin o le wi fun igi sikamine yi pe, Ki a fà ọ tú, ki a si gbìn ọ sinu okun; yio si gbọ́ ti nyin.

Òwe Iṣẹ́ Ọmọ-Ọ̀dọ̀

7 Ṣugbọn tani ninu nyin, ti o li ọmọ-ọdọ, ti o ntulẹ, tabi ti o mbọ́ ẹran, ti yio wi fun u lojukanna ti o ba ti oko de pe, Lọ ijoko lati jẹun? 8 Ti kì yio kuku wi fun u pe, Pèse ohun ti emi o jẹ, si di amure, ki iwọ ki o mã ṣe iranṣẹ fun mi, titi emi o fi jẹ ti emi o si mu tan; lẹhinna ni iwọ o si jẹ, ti iwọ o si mu? 9 On o ha ma dupẹ lọwọ ọmọ-ọdọ na, nitoriti o ṣe ohun ti a palaṣẹ fun u bi? emi kò rò bẹ̃. 10 Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu, nigbati ẹ ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun nyin tan, ẹ wipe, Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe.

Jesu Wo Àwọn Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn

11 O si ṣe, bi o ti nlọ si Jerusalemu, o kọja larin Samaria on Galili. 12 Bi o si ti nwọ̀ inu iletò kan lọ, awọn ọkunrin adẹtẹ̀ mẹwa pade rẹ̀, nwọn duro li òkere: 13 Nwọn si nahùn soke, wipe, Jesu, Olukọni ṣãnu fun wa. 14 Nigbati o ri wọn, o wi fun wọn pe, Ẹ lọ ifi ara nyin hàn fun awọn alufa. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, nwọn si di mimọ́. 15 Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo. 16 O si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o ndupẹ li ọwọ rẹ̀: ara Samaria ni on si iṣe. 17 Jesu si dahùn wipe, Awọn mẹwa ki a ṣo di mimọ́? Awọn mẹsan iyokù ha dà? 18 A ko ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikọse alejò yi? 19 O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.

Bí Ìjọba Yóo Ti Ṣe Dé

20 Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi: 21 Bẹ̃ni nwọn kì yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin. 22 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ọjọ mbọ̀, nigbati ẹnyin o fẹ lati ri ọkan ninu ọjọ Ọmọ-enia, ẹnyin kì yio si ri i. 23 Nwọn o si wi fun nyin pe, Wo o nihin; tabi wo o lọhun: ẹ má lọ, ẹ máṣe tẹle wọn. 24 Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ li apakan labẹ ọrun, ti isi mọlẹ li apa keji labẹ ọrun: bẹ̃li Ọmọ-enia yio si ri li ọjọ rẹ̀. 25 Ṣugbọn kò le ṣaima kọ́ jìya ohun pipo, ki a si kọ̀ ọ lọdọ iran yi. 26 Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹ̃ni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia. 27 Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ̀ inu ọkọ̀ lọ, kíkun omi si de, o si run gbogbo wọn. 28 Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Loti; nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn nrà, nwọn ntà, nwọn ngbìn, nwọn nkọle; 29 Ṣugbọn li ọjọ na ti Loti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ̀ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn. 30 Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ-enia yio farahàn. 31 Li ọjọ na, eniti o ba wà lori ile, ti ẹrù rẹ̀ si mbẹ ni ile, ki o máṣe sọkalẹ lati wá kó o; ẹniti o ba si wà li oko, ki o máṣe pada sẹhin. 32 Ẹ ranti aya Loti. 33 Ẹnikẹni ti o ba nwá ati gbà ẹmi rẹ̀ là yio sọ ọ nù; ẹnikẹni ti o ba si sọ ọ nù yio gbà a là. 34 Mo wi fun nyin, li oru ọjọ na, enia meji yio wà lori akete kan; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. 35 Enia meji yio si ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. 36 Enia meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. 37 Nwọn si da a lohùn, nwọn bi i pe, Nibo, Oluwa? O si wi fun wọn pe, Nibiti okú ba gbé wà, nibẹ̀ pẹlu ni idì ikojọ pọ̀ si.

Luku 18

Òwe Nípa Opó Kan ati Onidajọ

1 O si pa owe kan fun wọn nitori eyiyi pe, o yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ̀; 2 Wipe, Onidajọ́ kan wà ni ilu kan, ti kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti kò si ṣe ojusaju enia: 3 Opó kan si wà ni ilu na; o si ntọ̀ ọ wá, wipe, Gbẹsan mi lara ọtá mi. 4 Kò si ṣu si i nigba sã kan: ṣugbọn nikẹhin o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi emi kò tilẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ti emi ko si ṣe ojuṣãju enia; 5 Ṣugbọn nitoriti opó yi nyọ mi lẹnu, emi o gbẹsan rẹ̀, ki o má ba fi wíwa rẹ̀ nigbakugba da mi lagãra. 6 Oluwa si wipe, Ẹ gbọ́ bi alaiṣõtọ onidajọ ti wi. 7 Ọlọrun kì yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ̀, ti nfi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn? 8 Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?

Òwe Nípa Farisi Kan ati Agbowó-odè

9 O si pa owe yi fun awọn kan ti nwọn gbẹkẹle ara wọn pe, awọn li olododo, ti nwọn si ngàn awọn ẹlomiran: 10 Pe, Awọn ọkunrin meji goke lọ si tẹmpili lati gbadura; ọkan jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowode. 11 Eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara rẹ̀ bayi pe, Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi. 12 Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni. 13 Ṣugbọn agbowode duro li òkere, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ̀ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ. 14 Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ̀ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, on li a o rẹ̀ silẹ; ẹniti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ on li a o gbéga.

Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde

15 Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá pẹlu, ki o le fi ọwọ́ le wọn; ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, nwọn mba wọn wi. 16 Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun. 17 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù ki o ri. 18 Ijoye kan si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi jogún iye ainipẹkun? 19 Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si, bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun. 20 Iwọ mọ̀ ofin wọnni, Máṣe ṣe panṣaga, máṣe pania, máṣe jale, máṣe jẹri eke, bọ̀wọ fun baba on iya rẹ. 21 O si wipe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ti pamọ lati igba ewe mi wá. 22 Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin. 23 Nigbati o si gbọ́ eyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi: nitoriti o li ọrọ̀ pipo. 24 Nigbati Jesu ri i pe, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi, o ni, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! 25 Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. 26 Awọn ti o si gbọ́ wipe, Njẹ tali o ha le là? 27 O si wipe, Ohun ti o ṣoro lọdọ enia, kò ṣoro lọdọ Ọlọrun. 28 Peteru si wipe, Sawõ, awa ti fi tiwa silẹ, a si tọ̀ ọ lẹhin. 29 O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi õbi, tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun, 30 Ti kì yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

31 Nigbana li o pè awọn mejila sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Sawõ, awa ngòke lọ si Jerusalemu, a o si mu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ lati ọwọ́ awọn woli wá, nitori Ọmọ-enia. 32 Nitori a o fi i le awọn Keferi lọwọ, a o fi i ṣe ẹlẹyà, a o si fi i ṣe ẹsin, a o si tutọ́ si i lara: 33 Nwọn o si nà a, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde. 34 Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.

Jesu Wo Afọ́jú Alágbe Sàn Ní Jẹriko

35 O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe: 36 Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si. 37 Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ. 38 O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 39 Awọn ti nlọ niwaju ba a wi pe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i kunkun pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. 40 Jesu si dẹṣẹ duro, o ni, ki a mu u tọ̀ on wá: nigbati o si sunmọ ọ, o bi i, 41 Wipe, Kini iwọ nfẹ ti emi iba ṣe fun o? O si wipe, Oluwa, ki emi ki o le riran. 42 Jesu si wi fun u pe, Riran: igbagbọ́ rẹ gbà ọ là. 43 Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.

Luku 19

Jesu ati Sakiu

1 JESU si wọ̀ Jeriko lọ, o si nkọja lãrin rẹ̀. 2 Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ti a npè ni Sakeu, o si jẹ olori agbowode kan, o si jẹ ọlọrọ̀. 3 O si nfẹ lati ri ẹniti Jesu iṣe; kò si le ri i, nitori ọ̀pọ enia, ati nitoriti on ṣe enia kukuru. 4 O si sure siwaju, o gùn ori igi sikamore kan, ki o ba le ri i: nitoriti yio kọja lọ niha ibẹ̀. 5 Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni. 6 O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ̀ gbà a. 7 Nigbati nwọn si ri i, gbogbo wọn nkùn, wipe, O lọ iwọ̀ lọdọ ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ. 8 Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin. 9 Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu. 10 Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.

Òwe Nípa Owó Wúrà

11 Nigbati nwọn si ngbọ́ nkan wọnyi, o fi ọ̀rọ kún u, o si pa owe kan, nitoriti o sunmọ Jerusalemu, ati nitoriti nwọn nrò pe, ijọba Ọlọrun yio farahàn nisisiyi. 12 O si wipe, ọkunrin ọlọlá kan rè ilu òkere lọ igbà ijọba fun ara rẹ̀, ki o si pada. 13 O si pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ mẹwa, o fi mina mẹwa fun wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã ṣowo titi emi o fi de. 14 Ṣugbọn awọn ọlọ̀tọ ilu rẹ̀ korira rẹ̀, nwọn si rán ikọ̀ tẹ̀le e, wipe, Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa. 15 O si ṣe, nigbati o gbà ijọba tan, ti o pada de, o paṣẹ pe, ki a pè awọn ọmọ-ọdọ wọnni wá sọdọ rẹ̀, ti on ti fi owo fun nitori ki o le mọ̀ iye ere ti olukuluku fi iṣowo jẹ. 16 Eyi ekini si wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina mẹwa si i. 17 O si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa. 18 Eyi ekeji si wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina marun. 19 O si wi fun u pẹlu pe, Iwọ joye ilu marun. 20 Omiran si wá, o wipe, Oluwa, wò mina rẹ ti mbẹ li ọwọ́ mi ti mo dì sinu gèle: 21 Nitori mo bẹ̀ru rẹ, ati nitoriti iwọ ṣe onrorò enia: iwọ a ma mu eyi ti iwọ ko fi lelẹ, iwọ a si ma ká eyi ti iwọ kò gbìn. 22 O si wi fun u pe, Li ẹnu ara rẹ na li emi o ṣe idajọ rẹ, iwọ ọmọ-ọdọ buburu. Iwọ mọ̀ pe onrorò enia ni mi, pe, emi a ma mu eyi ti emi ko fi lelẹ emi a si ma ká eyi ti emi ko gbìn; 23 Ẽha si ti ṣe ti iwọ ko fi owo mi si ile elé, nigbati mo ba de, emi iba si bère rẹ̀ ti on ti elé? 24 O si wi fun awọn ti o duro leti ibẹ̀ pe, Ẹ gbà mina na lọwọ rẹ̀, ki ẹ si fi i fun ẹniti o ni mina mẹwa. 25 Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, o ni mina mẹwa. 26 Mo wi fun nyin pe, Ẹnikẹni ti o ni, li a o fifun; ati lọdọ ẹniti kò ni, eyi na ti o ni li a o gbà lọwọ rẹ̀. 27 Ṣugbọn awọn ọtá mi wọnni, ti kò fẹ ki emi ki o jọba lori wọn, ẹ mu wọn wá ihinyi, ki ẹ si pa wọn niwaju mi. 28 Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o lọ ṣaju, o ngòke lọ si Jerusalemu. 29 O si ṣe, nigbati o sunmọ Betfage on Betaní li òke ti a npè ni Olifi, o rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, 30 Wipe, Ẹ lọ iletò ti o kọju si nyin; nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ọ lọ, ẹnyin o ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn ri: ẹ tú u, ki ẹ si fà a wá. 31 Bi ẹnikẹni ba si bi nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú u? ki ẹnyin ki o wi bayi pe, Oluwa ni ifi i ṣe. 32 Awọn ti a rán si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti wi fun wọn. 33 Bi nwọn si ti ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, awọn oluwa rẹ̀ bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú kẹtẹkẹtẹ nì? 34 Nwọn si wipe, Oluwa ni ifi i ṣe. 35 Nwọn si fà a tọ̀ Jesu wá: nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, nwọn si gbé Jesu kà a. 36 Bi o si ti nlọ nwọn tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na. 37 Bi o si ti sunmọ eti ibẹ̀ ni gẹrẹgẹrẹ òke Olifi, gbogbo ijọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si iyọ̀, ati si ifi ohùn rara yìn Ọlọrun, nitori iṣẹ nla gbogbo ti nwọn ti ri; 38 Wipe, Olubukun li Ọba ti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun. 39 Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi. 40 O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.

Jesu Sọkún Lórí Jerusalẹmu

41 Nigbati o si sunmọ etile, o ṣijuwò ilu na, o sọkun si i lori, 42 O nwipe, Ibaṣepe iwọ mọ̀, loni yi, ani iwọ, ohun ti iṣe ti alafia rẹ! ṣugbọn nisisiyi nwọn pamọ́ kuro li oju rẹ. 43 Nitori ọjọ mbọ̀ fun ọ, ti awọn ọtá rẹ yio wà yàra ká ọ, nwọn o si yi ọ ká, nwọn o si ká ọ mọ́ niha gbogbo. 44 Nwọn o si wó ọ palẹ bẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; nwọn kì yio si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitoriti iwọ ko mọ̀ ọjọ ìbẹwo rẹ.

Jesu Lòdì sí Lílo Tẹmpili Bí Ọjà

45 O si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o si bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ninu rẹ̀ sode; 46 O si wi fun wọn pe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Ile mi yio jẹ ile adura; ṣugbọn ẹnyin ti sọ ọ di ihò olè. 47 O si nkọ́ni lojojumọ ni tẹmpili. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn olori awọn enia nwá ọ̀na ati pa a run, 48 Nwọn kò si ri bi nwọn iba ti ṣe: nitori gbogbo enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ̀rọ rẹ̀.

Luku 20

Ìbéèrè Nípa Àṣẹ Tí Jesu Ń Lò

1 O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i, 2 Nwọn si wi fun u pe, Sọ fun wa, aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tabi tali o fun ọ li aṣẹ yi? 3 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi pẹlu yio si bi nyin lẽre ọ̀rọ kan; ẹ sọ fun mi. 4 Baptismu ti Johanu, lati ọrun wá ni tabi lọdọ enia? 5 Nwọn si ba ara wọn gbèro wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni; on o wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a gbọ́? 6 Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; gbogbo enia ni yio sọ wa li okuta; nitori nwọn gbagbọ pe, woli ni Johanu. 7 Nwọn si dahùn wipe, nwọn kò mọ̀ ibiti o ti wá. 8 Jesu si wi fun wọn pe, Njẹ emi ki yio wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

Òwe Àwọn Alágbàro Kan ati Ọgbà Àjàrà

9 Nigbana li o bẹ̀rẹ si ipa owe yi fun awọn enia pe; ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si fi ṣe agbatọju fun awọn àgbẹ, o si lọ si àjo fun igba pipẹ. 10 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo. 11 O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo. 12 O si tún rán ẹkẹta: nwọn si ṣá a lọgbẹ pẹlu, nwọn si tì i jade. 13 Nigbana li oluwa ọgba ajara wipe, Ewo li emi o ṣe? emi o rán ọmọ mi ayanfẹ lọ: bọya nigbati nwọn ba ri i, nwọn o ṣojuṣaju fun u. 14 Ṣugbọn nigbati awọn àgbẹ na ri i, nwọn ba ara wọn gbèro pe, Eyi li arole: ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki ogún rẹ̀ ki o le jẹ ti wa. 15 Bẹ̃ni nwọn si ti i jade sẹhin ọgba ajara, nwọn si pa a. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe si wọn? 16 Yio wá, yio si pa awọn àgbẹ wọnni run, yio si fi ọgba ajara na fun awọn ẹlomiran. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn ni, Ki a má ri i. 17 Nigbati o si wò wọn, o ni, Ewo ha li eyi ti a ti kọwe pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li a sọ di pàtaki igun ile? 18 Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta na yio fọ́; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lulú. 19 Awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọna ati mu u ni wakati na; ṣugbọn nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitoriti nwọn mọ̀ pe, o pa owe yi mọ wọn.

Owó-Orí fún Kesari

20 Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ. 21 Nwọn si bi i, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe, iwọ a ma sọrọ fun ni, iwọ a si ma kọ́-ni bi o ti tọ, bẹ̃ni iwọ kì iṣojuṣaju ẹnikan ṣugbọn iwọ nkọ́-ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ. 22 O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? 23 Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? 24 Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni. 25 O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. 26 Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́.

Ìbéèrè nípa Ajinde Òkú

27 Awọn Sadusi kan si tọ̀ ọ wá, awọn ti nwọn nwipe ajinde okú kò si: nwọn si bi i, 28 Wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, li ailọmọ, ti o li aya, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe iru dide fun arakunrin rẹ̀. 29 Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: ekini gbé iyawo, o si kú li ailọmọ. 30 Ekeji si ṣu u lopó, on si kú li ailọmọ. 31 Ẹkẹta si ṣu u lopó; gẹgẹ bẹ̃ si li awọn mejeje pẹlu: nwọn kò si fi ọmọ silẹ, nwọn si kú. 32 Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. 33 Njẹ li ajinde okú, aya titani yio ha ṣe ninu wọn? nitori awọn mejeje li o sá ni i li aya. 34 Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Awọn ọmọ aiye yi a ma gbeyawo, nwọn a si ma fà iyawo fun-ni. 35 Ṣugbọn awọn ti a kà yẹ lati jogún aiye na, ati ajinde kuro ninu okú, nwọn kì igbeyawo, nwọn kì si ifà iyawo fun-ni: 36 Nitori nwọn kò le kú mọ́; nitoriti nwọn ba awọn angẹli dọgba; awọn ọmọ Ọlọrun si ni nwọn, nitori nwọn di awọn ọmọ ajinde. 37 Niti pe a njí awọn okú dide, Mose tikararẹ̀ si ti fihàn ni igbẹ́, nigbati o pè Oluwa ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. 38 Bẹni on kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye: nitori gbogbo wọn wà lãye fun u. 39 Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe da a lohùn, wipe, Olukọni iwọ wi rere. 40 Nwọn kò si jẹ bi i lẽre òrọ kan mọ́.

Ìbéèrè Nípa Ọmọ Dafidi

41 O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi? 42 Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, 43 Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. 44 Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀?

Jesu Bá Àwọn Akọ̀wé Wí

45 O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe, 46 Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse; 47 Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.

Luku 21

Ọrẹ Tí Opó Kan Ṣe

1 NIGBATI o si gbé oju soke, o ri awọn ọlọrọ̀ nfi ẹ̀bun wọn sinu apoti iṣura. 2 O si ri talakà opó kan pẹlu, o nsọ owo-idẹ wẹ́wẹ meji sibẹ. 3 O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ: 4 Nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu ẹ̀bun Ọlọrun lati ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aìni rẹ̀ o sọ gbogbo ohun ini rẹ̀ ti o ni sinu rẹ̀.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Pé A Óo Wó Tẹmpili

5 Bi awọn kan si ti nsọ̀rọ ti tẹmpili, bi a ti fi okuta daradara ati ẹ̀bun ṣe e li ọṣọ, o ní, 6 Ohun ti ẹnyin nwò wọnyi, ọjọ mbọ̀ li eyi ti a kì yio fi okuta kan silẹ lori ekeji ti a kì yio wó lulẹ.

Àwọn Àmì Àkókò Náà

7 Nwọn si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? ati àmi kini yio wà, nigbati nkan wọnyi yio fi ṣẹ? 8 O si wipe, Ẹ mã kiyesara, ki a má bà mu nyin ṣina: nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, ti yio mã wipe, Emi ni Kristi; akokò igbana si kù si dẹ̀dẹ: ẹ máṣe tọ̀ wọn lẹhin. 9 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gburó ogun ati idagìri, ẹ máṣe foiya: nitori nkan wọnyi ko le ṣe áìkọ́ṣẹ: ṣugbọn opin na kì iṣe lojukanna. 10 Nigbana li o wi fun wọn pe, Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: 11 Isẹlẹ nla yio si wà kakiri, ati ìyan ati ajakalẹ arùn; ohun ẹ̀ru, ati àmi nla yio si ti ọrun wá. 12 Ṣugbọn ṣaju gbogbo nkan wọnyi, nwọn o nawọ́ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi. 13 Yio si pada di ẹrí fun nyin. 14 Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun. 15 Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju. 16 A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin. 17 A o si korira nyin lọdọ gbogbo enia nitori orukọ mi. 18 Ṣugbọn irun ori nyin kan kì o ṣegbé. 19 Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Pé Ogun Yóo Kó Ìlú Jerusalẹmu

20 Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nigbana pe, isọdahoro rẹ̀ kù si dẹ̀dẹ. 21 Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sá lọ sori òke; ati awọn ti mbẹ larin rẹ̀ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ̀ inu rẹ̀ lọ. 22 Nitori ọjọ ẹsan li ọjọ wọnni, ki a le mu ohun gbogbo ti a ti kọwe rẹ̀ ṣẹ. 23 Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! nitoriti ipọnju pipọ yio wà lori ati ibinu si awọn enia wọnyi. 24 Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún.

Àkókò Tí Ọmọ-Eniyan Yóo Dé

25 Àmi yio si wà li õrùn, ati li oṣupa, ati ni irawọ; ati lori ilẹ aiye idamu fun awọn orilẹ-ede nitori ipaiya ti ariwo; 26 Aiya awọn enia yio ma já fun ibẹru, ati fun ireti nkan wọnni ti mbọ̀ sori aiye: nitori awọn agbara ọrun li a o mì titi. 27 Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla. 28 Ṣugbọn nigbati nkan wọnyi ba bẹ̀rẹ si iṣẹ, njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹ̀dẹ.

Ẹ̀kọ́ Tí Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kọ́ni

29 O si pa owe kan fun wọn pe; Ẹ kiyesi igi ọpọtọ, ati si gbogbo igi; 30 Nigbati nwọn ba rúwe, ẹnyin ri i, ẹ si mọ̀ fun ara nyin pe, igba ẹ̀run kù fẹfẹ. 31 Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù si dẹ̀dẹ. 32 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. 33 Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Ẹ Ṣọ́ra

34 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun. 35 Nitori bẹni yio de ba gbogbo awọn ti ngbe ori gbogbo ilẹ aiye. 36 Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le là gbogbo nkan wọnyi ti mbọ̀ wá iṣẹ, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ-enia. 37 Lọsán, a si ma kọ́ni ni tẹmpili; loru, a si ma jade lọ iwọ̀ lori òke ti a npè ni oke Olifi. 38 Gbogbo enia si ntọ̀ ọ wá ni tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, lati gbọ́rọ rẹ̀.

Luku 22

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu

1 AJỌ ọdun aiwukara ti a npè ni Irekọja si kù fẹfẹ. 2 Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia. 3 Satani si wọ̀ inu Judasi, ti a npè ni Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila. 4 O si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o lọ lati ba awọn olori alufa ati awọn olori ẹṣọ́ mọ̀ ọ pọ̀, bi on iba ti fi i le wọn lọwọ. 5 Nwọn si yọ̀, nwọn si ba a da majẹmu ati fun u li owo. 6 O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo.

Ìpalẹ̀mọ́ fún Àsè Ìrékọjá

7 Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. 8 O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. 9 Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? 10 O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. 11 Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? 12 On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ. 13 Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

14 Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀. 15 O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya: 16 Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun. 17 O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin. 18 Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de. 19 O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. 20 Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin. 21 Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili. 22 Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn! 23 Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi. 24 Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn. 25 O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre. 26 Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ. 27 Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ. 28 Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. 29 Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; 30 Ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ́, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹ̀ya Israeli mejila.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun

31 Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: 32 Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. 33 O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú. 34 O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi.

Idà Meji

35 O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o. 36 Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan. 37 Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin. 38 Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to.

Adura Lórí Òkè Olifi

39 O si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. 40 Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. 41 O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, 42 Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. 43 Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. 44 Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. 45 Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, 46 O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò.

Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

47 Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. 48 Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn? 49 Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn? 50 Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù. 51 Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn. 52 Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá? 53 Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.

Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

54 Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere. 55 Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn. 56 Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀. 57 O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ. 58 Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ. 59 O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe. 60 Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ. 61 Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta. 62 Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò.

Wọ́n Fi Jesu Ṣẹ̀sín

63 Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u. 64 Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì? 65 Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i.

Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀

66 Nigbati ilẹ si mọ́, awọn àgba awọn enia, ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe pejọ, nwọn si fà a wá si ajọ wọn, nwọn nwipe, 67 Bi iwọ ba iṣe Kristi na? sọ fun wa. O si wi fun wọn pe, Bi mo ba wi fun nyin, ẹnyin ki yio gbagbọ́: 68 Bi mo ba si bi nyin lẽre pẹlu, ẹnyin kì yio da mi lohùn, bẹ̃li ẹnyin kì yio jọwọ mi lọwọ lọ. 69 Ṣugbọn lati isisiyi lọ li Ọmọ-enia yio joko li ọwọ́ ọtún agbara Ọlọrun. 70 Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni. 71 Nwọn si wipe, Kili awa nfẹ ẹlẹri mọ́ si? Awa tikarawa sá ti gbọ́ li ẹnu ara rẹ̀.

Luku 23

Wọ́n Fa Jesu Lọ Siwaju Pilatu

1 GBOGBO ijọ enia si dide, nwọn si fà a lọ si ọdọ Pilatu. 2 Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba. 3 Pilatu si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li ọba awọn Ju? O si da a lohùn wipe, Iwọ wi i. 4 Pilatu si wi fun awọn olori alufa ati fun ijọ enia pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi. 5 Nwọn si tubọ tẹnumọ ọ pe, O nrú awọn enia soke, o nkọ́ni ká gbogbo Judea, o bẹ̀rẹ lati Galili wá titi o fi de ihinyi. 6 Nigbati Pilatu gbọ́ orukọ Galili, o bère bi ọkunrin na iṣe ara Galili. 7 Nigbati o si mọ̀ pe ara ilẹ Herodu ni, o rán a si Herodu, ẹniti on tikararẹ̀ wà ni Jerusalemu li akokò na. 8 Nigbati Herodu si ri Jesu, o yọ̀ gidigidi: nitoriti o ti nfẹ ẹ ri pẹ́, o sa ti ngbọ́ ìhin pipọ nitori rẹ̀; o si tanmọ̃ ati ri ki iṣẹ iyanu diẹ ki o ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe. 9 O si bère ọ̀rọ pipọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn kò da a lohùn kanṣoṣo. 10 Ati awọn olori alufa ati awọn akọwe duro, nwọn si nfi i sùn gidigidi. 11 Ati Herodu ti on ti awọn ọmọ-ogun rẹ̀, nwọn kẹgan rẹ̀, nwọn si nfi i ṣẹsin, nwọn wọ̀ ọ li aṣọ daradara, o si rán a pada tọ̀ Pilatu lọ. 12 Pilatu on Herodu di ọrẹ́ ara wọn ni ijọ na: nitori latijọ ọtá ara wọn ni nwọn ti nṣe ri.

A Dá Jesu Lẹ́bi Ikú

13 Nigbati Pilatu si ti pè awọn olori alufa ati awọn olori ati awọn enia jọ, 14 O sọ fun wọn pe, Ẹnyin mu ọkunrin yi tọ̀ mi wá, bi ẹni ti o npa awọn enia li ọkàn dà: si kiyesi i, emi wadi ẹjọ rẹ̀ niwaju nyin, emi kò si ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi, ni gbogbo nkan wọnyi ti ẹnyin fi i sùn si: 15 Ati Herodu pẹlu: o sá rán a pada tọ̀ wa wá; si kiyesi i, ohun kan ti o yẹ si ikú a ko ṣe si i ti ọwọ́ rẹ̀ wá. 16 Njẹ emi ó nà a, emi ó si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. 17 Ṣugbọn kò le ṣe aidá ọkan silẹ fun wọn nigba ajọ irekọja. 18 Nwọn si kigbe soke lọwọ kanna, wipe, Mu ọkunrin yi kuro, ki o si dá Barabba silẹ fun wa: 19 Ẹniti a sọ sinu tubu nitori ọ̀tẹ kan ti a ṣe ni ilu, ati nitori ipania. 20 Pilatu si tun ba wọn sọrọ, nitori o fẹ da Jesu silẹ. 21 Ṣugbọn nwọn kigbe, wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. 22 O si wi fun wọn li ẹrinkẹta pe, Ẽṣe, buburu kili ọkunrin yi ṣe? emi ko ri ọ̀ran ikú lara rẹ̀: nitorina emi o nà a, emi a si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. 23 Nwọn tilẹ̀ kirimọ́ igbe nla, nwọn nfẹ ki a kàn a mọ agbelebu. Ohùn ti wọn ati ti awọn olori alufa bori tirẹ̀. 24 Pilatu si fi aṣẹ si i pe, ki o ri bi nwọn ti nfẹ. 25 O si dá ẹniti nwọn fẹ silẹ fun wọn, ẹniti a titori ọ̀tẹ ati ipania sọ sinu tubu; ṣugbọn o fi Jesu le wọn lọwọ.

A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

26 Bi nwọn si ti nfà a lọ, nwọn mu ọkunrin kan, Simoni ara Kirene, ti o nti igberiko bọ̀, on ni nwọn si gbé agbelebu na le, ki o mã rù u bọ̀ tẹle Jesu. 27 Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀. 28 Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin. 29 Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri. 30 Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ. 31 Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ? 32 Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀. 33 Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi. 34 Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀. 35 Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun. 36 Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u, 37 Nwọn si nwipe, Bi iwọ ba ṣe Ọba awọn Ju, gbà ara rẹ là. 38 Nwọn si kọwe akọlé si ìgbèri rẹ̀ ni ède Hellene, ati ti Latini, ati ti Heberu, EYI LI ỌBA AWỌN JU. 39 Ati ọkan ninu awọn arufin ti a gbe kọ́ nfi ṣe ẹlẹyà wipe, Bi iwọ ba ṣe Kristi, gbà ara rẹ ati awa là. 40 Ṣugbọn eyi ekeji dahùn, o mba a wipe, Iwọ kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti iwọ wà ninu ẹbi kanna? 41 Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan. 42 O si wipe, Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ. 43 Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ, Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.

Ikú Jesu

44 O si to ìwọn wakati kẹfa ọjọ, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan ọjọ. 45 Õrùn si ṣú õkun, aṣọ ikele ti tẹmpili si ya li agbedemeji. 46 Nigbati Jesu si kigbe li ohùn rara, o ni, Baba, li ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹmí mi le: nigbati o si wi eyi tan, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. 47 Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi. 48 Gbogbo ijọ enia ti o pejọ si iran yi, nigbati nwọn nwò ohun ti nṣe, nwọn a lù ara wọn li õkan àiya, nwọn a si pada. 49 Ati gbogbo awọn ojulumọ̀ rẹ̀, ati awọn obinrin ti ntọ̀ ọ lẹhin lati Galili wá, nwọn duro li òkere, nwọn nwò nkan wọnyi.

Ìsìnkú Jesu

50 Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Josefu, ìgbimọ, enia rere, ati olõtọ, 51 (On kò ba wọn li ohùn ni ìmọ ati iṣe wọn), ara Arimatea, ilu awọn Ju kan, ẹniti on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun; 52 Ọkunrin yi tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. 53 Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. 54 O si ṣe ọjọ Ipalẹmọ: ọjọ isimi si kù si dẹ̀dẹ. 55 Ati awọn obinrin, ti nwọn bá a ti Galili wá, ti nwọn si tẹle, nwọn kiyesi ibojì na, ati bi a ti tẹ́ okú rẹ̀ si. 56 Nigbati nwọn si pada, nwọn pèse ohun olõrun didùn ororo ikunra ati turari tutù; nwọn si simi li ọjọ isimi gẹgẹ bi ofin.

Luku 24

Ajinde Jesu

1 Ni ijọ kini ọ̀sẹ, ni kutukutu owurọ̀, nwọn wá si ibojì, nwọn nmu turari wá ti nwọn ti pèse silẹ, ati awọn miran kan pẹlu wọn. 2 Nwọn si ba a, a ti yi okuta kuro li ẹnu ibojì. 3 Nigbati nwọn wọ̀ inu rẹ̀, nwọn kò si ri okú Jesu Oluwa. 4 O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn: 5 Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú? 6 Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili, 7 Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde. 8 Nwọn si ranti ọ̀rọ rẹ̀. 9 Nwọn si pada ti ibojì wá, nwọn si ròhin gbogbo nkan wọnyi fun awọn mọkanla, ati fun gbogbo awọn iyokù. 10 Maria Magdalene, ati Joanna, ati Maria, iya Jakọbu, ati awọn omiran pẹlu wọn si ni, ti nwọn ròhin nkan wọnyi fun awọn aposteli. 11 Ọ̀rọ wọnyi si dabi isọkusọ loju wọn, nwọn kò si gbà wọn gbọ́. 12 Nigbana ni Peteru dide, o sure lọ si ibojì; nigbati o si bẹ̀rẹ, o ri aṣọ àla li ọ̀tọ fun ara wọn, o si pada lọ ile rẹ̀, ẹnu yà a si ohun ti o ṣe.

Ìrìn àjò Lọ́nà Emmausi

13 Si kiyesi i, awọn meji ninu wọn nlọ ni ijọ na si iletò kan ti a npè ni Emmausi, ti o jina si Jerusalemu niwọn ọgọta furlongi. 14 Nwọn mba ara wọn sọ̀rọ gbogbo nkan wọnyi ti o ṣẹlẹ̀. 15 O si ṣe, nigbati nwọn mba ara wọn sọ, ti nwọn si mba ara wọn jirorò, Jesu tikararẹ̀ sunmọ wọn, o si mba wọn rìn lọ. 16 Ṣugbọn a rú wọn li oju ki nwọn ki o máṣe le mọ̀ ọ. 17 O si bi wọn pe, Ọ̀rọ kili ẹnyin mba ara nyin sọ, bi ẹnyin ti nrìn? Nwọn si duro jẹ, nwọn fajuro. 18 Ọkan ninu wọn, ti a npè ni Kleopa, si dahùn wi fun u pe, Alejò ṣá ni iwọ ni Jerusalemu, ti iwọ kò si mọ̀ ohun ti o ṣe nibẹ̀ li ọjọ wọnyi? 19 O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia: 20 Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu. 21 Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ. 22 Awọn obinrin kan pẹlu li ẹgbẹ wa, ti nwọn lọ si ibojì ni kutukutu, si wá idá wa nijì; 23 Nigbati nwọn kò si ri okú rẹ̀, nwọn wá wipe, awọn ri iran awọn angẹli ti nwọn wipe, o wà lãye. 24 Ati awọn kan ti nwọn wà pẹlu wa lọ si ibojì, nwọn si ri i gẹgẹ bi awọn obinrin ti wi: ṣugbọn on tikararẹ̀ ni nwọn kò ri. 25 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́: 26 Ko ha yẹ ki Kristi ki o jìya nkan wọnyi ki o si wọ̀ inu ogo rẹ̀ lọ? 27 O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀. 28 Nwọn si sunmọ iletò ti nwọn nlọ: o si ṣe bi ẹnipe yio lọ si iwaju. 29 Nwọn si rọ̀ ọ, wipe, Ba wa duro: nitori o di ọjọ alẹ, ọjọ si kọja tan. O si wọle lọ, o ba wọn duro. 30 O si ṣe, bi o ti ba wọn joko tì onjẹ, o mu àkara, o sure si i, o si bù u, o si fifun wọn. 31 Oju wọn si là, nwọn si mọ̀ ọ; o si nù mọ wọn li oju. 32 Nwọn si ba ara wọn sọ pe, Ọkàn wa kò ha gbiná ninu wa, nigbati o mba wa sọ̀rọ li ọna, ati nigbati o ntumọ̀ iwe-mimọ́ fun wa? 33 Nwọn si dide ni wakati kanna, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si ba awọn mọkanla pejọ, ati awọn ti mbẹ lọdọ wọn, 34 Nwipe, Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni. 35 Nwọn si ròhin nkan ti o ṣe li ọ̀na, ati bi o ti di mimọ̀ fun wọn ni bibu àkara.

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀

36 Bi nwọn si ti nsọ nkan wọnyi, Jesu tikararẹ̀ duro li arin wọn, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin. 37 Ṣugbọn àiya fò wọn, nwọn si dijì, nwọn ṣebi awọn rí iwin. 38 O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ara nyin kò lelẹ̀? ẽsitiṣe ti ìrokuro fi nsọ ninu ọkàn nyin? 39 Ẹ wò ọwọ́ mi ati ẹsẹ mi, pe emi tikarami ni: ẹ dì mi mu ki ẹ wò o; nitoriti iwin kò li ẹran on egungun lara, bi ẹnyin ti ri ti mo ni. 40 Nigbati o si wi bẹ̃ tán, o fi ọwọ́ on ẹsẹ rẹ̀ hàn wọn. 41 Nigbati nwọn kò si tí igbagbọ́ fun ayọ̀, ati fun iyanu, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ni ohunkohun jijẹ nihinyi? 42 Nwọn si fun u li ẹja bibu, ati afára oyin diẹ. 43 O si gba a, o jẹ ẹ loju wọn. 44 O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi. 45 Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn, 46 O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú: 47 Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ. 48 Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi. 49 Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá.

Jesu Gòkè Re Ọ̀run

50 O si mu wọn jade lọ titi nwọn fẹrẹ̀ de Betani, nigbati o si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o sure fun wọn. 51 O si ṣe, bi o ti nsure fun wọn, a yà a kuro lọdọ wọn, a si gbé e lọ si ọrun. 52 Nwọn si foribalẹ̀ fun u, nwọn si pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀ pipọ: 53 Nwọn si wà ni tẹmpili nigbagbogbo, nwọn mbu iyin, nwọn si nfi ibukun fun Ọlọrun. Amin.

Johanu 1

Ọlọrun di Eniyan

1 LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na. 2 On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun. 3 Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. 4 Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye. 5 Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀. 6 Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu. 7 On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀. 8 On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na. 9 Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye. 10 On si wà li aiye, nipasẹ rẹ̀ li a si ti da aiye, aiye kò si mọ̀ ọ. 11 O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a. 12 Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́: 13 Awọn ẹniti a bí, kì iṣe nipa ti ẹ̀jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹ̃ni kì iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun. 14 Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ. 15 Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi. 16 Nitori ninu ẹkún rẹ̀ ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ. 17 Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá. 18 Ko si ẹniti o ri Ọlọrun rí; Ọmọ bíbi kanṣoṣo, ti mbẹ li õkan àiya Baba, on na li o fi i hàn.

Ẹ̀rí Johanu Onítẹ̀bọmi nípa Jesu

19 Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe? 20 O si jẹwọ, kò si sẹ́; o si jẹwọ pe, Emi kì iṣe Kristi na. 21 Nwọn si bi i pe, Tani iwọ ha iṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹ̃kọ. Iwọ ni woli na bi? O si dahùn wipe, Bẹ̃kọ. 22 Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? ki awa ki o le fi èsi fun awọn ti o rán wa. Kili o wi ni ti ara rẹ? 23 O wipe, Emi li ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ ṣe ki ọ̀na Oluwa tọ́, gẹgẹ bi woli Isaiah ti wi. 24 Awọn ti a rán si jẹ ninu awọn Farisi. 25 Nwọn si bi i lẽre, nwọn si wi fun u pe, Njẹ ẽṣe ti iwọ fi mbaptisi, bi iwọ kì ibá ṣe Kristi na, tabi Elijah, tabi woli na? 26 Johanu da wọn lohùn, wipe, Emi nfi omi baptisi: ẹnikan duro larin nyin, ẹniti ẹnyin kò mọ̀; 27 On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀. 28 Nkan wọnyi li a ṣe ni Betani loke odò Jordani, nibiti Johanu gbé mbaptisi.

Ọ̀dọ́ Aguntan Ọlọrun Farahàn

29 Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ! 30 Eyi li ẹniti mo ti wipe, ọkunrin kan mbọ̀ wá lẹhin mi, ẹniti o pọ̀ju mi lọ: nitoriti o ti wà ṣiwaju mi. 31 Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ki a le fi i hàn fun Israeli, nitorina li emi ṣe wá ti mo nfi omi baptisi. 32 Johanu si jẹri, o wipe, mo ri Ẹmi sọkalẹ lati ọrun wá bi àdaba, o si bà le e. 33 Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹniti o rán mi wá, lati fi omi baptisi, on na li o wi fun mi pe, Lori ẹniti iwọ ba ri, ti Ẹmí sọkalẹ si, ti o si bà le e, on na li ẹniti nfi Ẹmí Mimọ́ baptisi. 34 Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.

Àwọn Ọmọ-Ẹ̀hìn Kinni tí Jesu Ní

35 Ni ijọ keji ẹwẹ Johanu duro, ati meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: 36 O si wò Jesu bi o ti nrìn, o si wipe, Wò Ọdọ-agutan Ọlọrun! 37 Awọn ọmọ-ẹhin meji na si gbọ́ nigbati o wi, nwọn si tọ̀ Jesu lẹhin. 38 Nigbana ni Jesu yipada, o ri nwọn ntọ̀ on lẹhin, o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nwá? Nwọn wi fun u pe, Rabbi, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Olukọni,) nibo ni iwọ ngbé? 39 O wi fun wọn pe, Ẹ wá wò o. Nwọn si wá, nwọn si ri ibi ti o ngbé, nwọn si ba a joko ni ijọ na: nitoriti o jẹ ìwọn wakati kẹwa ọjọ. 40 Ọkan ninu awọn meji ti o gbọ́ ọ̀rọ Johanu, ti o si tọ̀ Jesu lẹhin, ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru. 41 On tètekọ ri Simoni arakunrin on tikararẹ̀, o si wi fun u pe, Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyi ti ijẹ Kristi. 42 O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.

Jesu Pe Filipi ati Natanaeli

43 Ni ọjọ keji Jesu nfẹ jade lọ si Galili, o si ri Filippi, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. 44 Ara Betsaida ni Filippi iṣe, ilu Anderu ati Peteru. 45 Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu. 46 Natanaeli si wi fun u pe, Ohun rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi wi fun u pe, Wá wò o. 47 Jesu ri Natanaeli mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀, o si wi nipa rẹ̀ pe, Wo o, ọmọ Israelì nitõtọ, ninu ẹniti ẹ̀tan kò si! 48 Natanaeli wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti mọ̀ mi? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ki Filippi to pè ọ, nigbati iwọ wà labẹ igi ọ̀pọ́tọ, mo ti ri ọ. 49 Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli. 50 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Nitori mo wi fun ọ pe, mo ri ọ labẹ igi ọpọtọ ni iwọ ṣe gbagbọ? iwọ ó ri ohun ti o pọ̀ju wọnyi lọ. 51 O si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin o ri ọrun ṣí silẹ, awọn angẹli Ọlọrun yio si ma gòke, nwọn o si ma sọkalẹ sori Ọmọ-enia.

Johanu 2

Jesu Lọ sí Ibi Igbeyawo Kan ní Kana

1 NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀: 2 A si pè Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu, si ibi igbeyawo. 3 Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini. 4 Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de. 5 Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e. 6 Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta. 7 Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti. 8 O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ. 9 Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo, 10 O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi. 11 Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́. 12 Lẹhin eyi, o sọkalẹ lọ si Kapernamu, on ati iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nwọn kò si gbé ibẹ̀ li ọjọ pupọ.

Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà

13 Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu, 14 O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko: 15 O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu. 16 O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità. 17 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ranti pe, a ti kọ ọ pe, Itara ile rẹ jẹ mi run. 18 Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi? 19 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ wó tẹmpili yi palẹ̀, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró. 20 Nigbana li awọn Ju wipe, Ọdún mẹrindiladọta li a fi kọ́ tẹmpili yi, iwọ o ha si gbé e ró ni ijọ mẹta? 21 Ṣugbọn on nsọ ti tẹmpili ara rẹ̀. 22 Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ.

Jesu Mọ Inú Gbogbo Eniyan

23 Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni ajọ irekọja, lakoko ajọ na, ọ̀pọ enia gbà orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀ ti o ṣe. 24 Ṣugbọn Jesu kò gbé ara le wọn, nitoriti o mọ̀ gbogbo enia. 25 On ko si wa ki ẹnikẹni ki o jẹri enia fun on: nitoriti on mọ̀ ohun ti mbẹ ninu enia.

Johanu 3

Jesu ati Nikodemu

1 ỌKUNRIN kan si wà ninu awọn Farisi, ti a npè ni Nikodemu, ijoye kan ninu awọn Ju: 2 On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. 3 Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun. 4 Nikodemu wi fun u pe, A o ti ṣe le tún enia bí, nigbati o di agbalagba tan? o ha le wọ̀ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, ki a si bí i? 5 Jesu dahùn wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a fi omi ati Ẹmi bi enia, on kò le wọ̀ ijọba Ọlọrun. 6 Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni. 7 Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitún nyin bí. 8 Afẹfẹ nfẹ si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iró rẹ̀, ṣugbọn iwọ kò mọ̀ ibi ti o ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bẹ̃ni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmí. 9 Nikodemu dahùn, o si wi fun u pe, Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ̃? 10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi? 11 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Awa nsọ eyiti awa mọ̀, a si njẹri eyiti awa ti ri; ẹnyin kò si gbà ẹri wa. 12 Bi mo ba sọ̀ ohun ti aiye yi fun nyin, ti ẹnyin kò si gbagbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbagbọ́ bi mo ba sọ ohun ti ọrun fun nyin? 13 Ko si si ẹniti o gòke re ọrun, bikoṣe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ-enia ti mbẹ li ọrun. 14 Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu: 15 Ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, ki o má ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun. 16 Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun. 17 Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là. 18 Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́. 19 Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru. 20 Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí. 21 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.

Johanu Tún Sọ̀rọ̀ nípa Jesu

22 Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá si ilẹ Judea; o si duro pẹlu wọn nibẹ o si baptisi. 23 Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn. 24 Nitoriti a kò ti isọ Johanu sinu tubu. 25 Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu. 26 Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá. 27 Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá. 28 Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀. 29 Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun. 30 On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.

Ipò Ẹni Tí Ó Wá láti Ọ̀run

31 Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ. 32 Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀. 33 Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun. 34 Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn. 35 Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ. 36 Ẹniti o ba gbà Ọmọ gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀.

Johanu 4

Jesu Bá Obinrin Ará Samaria Sọ̀rọ̀

1 NITORINA nigbati Oluwa ti mọ̀ bi awọn Farisi ti gbọ́ pe, Jesu nṣe o si mbaptisi awọn ọmọ-ẹhin pupọ jù Johanu lọ, 2 (Ṣugbọn Jesu tikararẹ̀ kò baptisi bikoṣe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,) 3 O fi Judea silẹ, o si tún lọ si Galili. 4 On kò si le ṣaima kọja lãrin Samaria. 5 Nigbana li o de ilu Samaria kan, ti a npè ni Sikari, ti o sunmọ eti ilẹ biri nì, ti Jakọbu ti fifun Josefu, ọmọ rẹ̀. 6 Kanga Jakọbu si wà nibẹ̀. Nitorina bi o ti rẹ̀ Jesu tan nitori ìrin rẹ̀, bẹ̀li o joko leti kanga: o si jẹ ìwọn wakati kẹfa ọjọ. 7 Obinrin kan, ara Samaria, si wá lati pọn omi: Jesu wi fun u pe, Fun mi mu. 8 (Nitori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti lọ si ilu lọ irà onjẹ.) 9 Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀. 10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ. 11 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na? 12 Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀? 13 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ: 14 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun. 15 Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin. 16 Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi. 17 Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ: 18 Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini. 19 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe. 20 Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn. 21 Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba. 22 Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá. 23 Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on. 24 Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ. 25 Obinrin na wi fun u pe, mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa. 26 Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on. 27 Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ? 28 Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, 29 Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na? 30 Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá. 31 Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun. 32 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀. 33 Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi? 34 Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀. 35 Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na. 36 Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀. 37 Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ. 38 Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ. 39 Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi. 40 Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji. 41 Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀; 42 Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.

Jesu Wo Ọmọ Ìjòyè kan Sàn

43 Lẹhin ijọ meji o si ti ibẹ̀ kuro, o lọ si Galili. 44 Nitori Jesu tikararẹ̀ ti jẹri wipe, Woli ki ini ọlá ni ilẹ on tikararẹ̀. 45 Nitorina nigbati o de Galili, awọn ara Galili gbà a, nitoriti nwọn ti ri ohun gbogbo ti o ṣe ni Jerusalemu nigba ajọ; nitori awọn tikarawọn lọ si ajọ pẹlu. 46 Bẹ̃ni Jesu tún wà si Kana ti Galili, nibiti o gbé sọ omi di waini. ọkunrin ọlọla kan si wà, ẹniti ara ọmọ rẹ̀ kò da ni Kapernaumu. 47 Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú. 48 Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Bikoṣepe ẹnyin ba ri àmi ati iṣẹ iyanu, ẹnyin kì yio gbagbọ́ lai. 49 Ọkunrin ọlọla na wi fun u pe, Oluwa, sọkalẹ wá, ki ọmọ mi ki o to ku. 50 Jesu wi fun u pe, Mã ba ọ̀na rẹ lọ; ọmọ rẹ yè. ọkunrin na si gbà ọ̀rọ ti Jesu sọ fun u gbọ́, o si lọ. 51 Bi o si ti nsọkalẹ lọ, awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pade rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, ọmọ rẹ yè. 52 Nigbana li o bère wakati ti o bẹ̀rẹ si isàn lọwọ wọn. Nwọn si wi fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni ibà na fi i silẹ. 53 Bẹ̃ni baba na mọ̀ pe, ni wakati kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe, Ọmọ rẹ yè: on tikararẹ̀ si gbagbọ́, ati gbogbo ile rẹ̀. 54 Eyi ni iṣẹ́ ami keji, ti Jesu ṣe nigbati o ti Judea jade wá si Galili.

Johanu 5

Jesu wo Arọ kan Sàn ní Jerusalẹmu

1 LẸHIN nkan wọnyi ajọ awọn Ju kan kò; Jesu si gòke lọ si Jerusalemu. 2 Adagun omi kan si wà ni Jerusalemu, leti bodè agutan, ti a npè ni Betesda li ède Heberu, ti o ni iloro marun. 3 Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi. 4 Nitori angẹli a ma digbà sọkalẹ lọ sinu adagun na, a si ma rú omi: lẹhin igbati a ba ti rú omi na tan ẹnikẹni ti o ba kọ́ wọ̀ inu rẹ̀, a di alaradidá ninu arùnkárun ti o ni. 5 Ọkunrin kan si wà nibẹ̀, ẹniti o wà ni ailera rẹ̀ li ọdún mejidilogoji. 6 Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi? 7 Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi. 8 Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin. 9 Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi. 10 Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ. 11 O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn. 12 Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si ma rìn? 13 Ẹniti a mu larada na kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuto nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀. 14 Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ. 15 Ọkunrin na lọ, o si sọ fun awọn Ju pe, Jesu li ẹniti o mu on larada. 16 Nitori eyi li awọn Ju si nṣe inunibini si Jesu, nwọn si nwá ọ̀na ati pa a, nitoriti a nṣe nkan wọnyi li ọjọ isimi. 17 Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ. 18 Nitori eyi li awọn Ju tubọ nwá ọ̀na ati pa a, ki iṣe nitoripe o ba ọjọ isimi jẹ nikan ni, ṣugbọn o wi pẹlu pe, Baba on li Ọlọrun iṣe, o nmu ara rẹ̀ ba Ọlọrun dọgba.

Àṣẹ tí Jesu fi ń Ṣiṣẹ́

19 Nigbana ni Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ kò le ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi li Ọmọ si nṣe bẹ̃ gẹgẹ. 20 Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin. 21 Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti njí okú dide, ti o si nsọ wọn di ãye; bẹ̃li Ọmọ si nsọ awọn ti o fẹ di ãye. 22 Nitoripe Baba ki iṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ: 23 Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a. 24 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ mi, ti o ba si gbà ẹniti o rán mi gbọ́, o ni iye ti kò nipẹkun, on kì yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si ìye. 25 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè. 26 Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀; 27 O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia. 28 Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀. 29 Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jesu

30 Emi kò le ṣe ohun kan fun ara mi: bi mo ti ngbọ́, mo ndajọ: ododo si ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. 31 Bi emi ba njẹri ara mi, ẹrí mi kì iṣe otitọ. 32 Ẹlomiran li ẹniti njẹri mi; emi si mọ̀ pe, otitọ li ẹrí mi ti o jẹ́. 33 Ẹnyin ti ranṣẹ lọ sọdọ Johanu, on si ti jẹri si otitọ. 34 Ṣugbọn emi kò gba ẹrí lọdọ enia: ṣugbọn nkan wọnyi li emi nsọ, ki ẹnyin ki o le là. 35 On ni fitila ti o njó, ti o si ntànmọlẹ: ẹnyin si fẹ fun sã kan lati mã yọ̀ ninu imọlẹ rẹ̀. 36 Ṣugbọn emi ni ẹri ti o pọ̀ju ti Johanu lọ: nitori iṣẹ ti Baba ti fifun mi lati ṣe pari, iṣẹ na pãpã ti emi nṣe ni njẹri mi pe, Baba li o rán mi. 37 Ati Baba ti o rán mi ti jẹri mi. Ẹnyin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nigba kan ri, bẹ̃li ẹ kò ri àwọ rẹ̀. 38 Ẹ kò si ni ọ̀rọ rẹ̀ lati ma gbé inu nyin: nitori ẹniti o rán, on li ẹnyin kò gbagbọ́. 39 Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ́ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni ìye ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi. 40 Ẹnyin kò si fẹ lati wá sọdọ mi, ki ẹnyin ki o le ni ìye. 41 Emi kò gbà ogo lọdọ enia. 42 Ṣugbọn emi mọ̀ nyin pe, ẹnyin tikaranyin kò ni ifẹ Ọlọrun ninu nyin. 43 Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà. 44 Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá? 45 Ẹ máṣe rò pe, emi ó fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle. 46 Nitoripe ẹnyin iba gbà Mose gbọ́, ẹnyin iba gbà mi gbọ́: nitori o kọ iwe nipa ti emi. 47 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbà iwe rẹ̀ gbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbà ọ̀rọ mi gbọ́?

Johanu 6

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

1 LẸHIN nkan wọnyi, Jesu kọja si apakeji okun Galili, ti iṣe okun Tiberia. 2 Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn. 3 Jesu si gùn ori òke lọ, nibẹ̀ li o si gbé joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 4 Ajọ irekọja, ọdun awọn Ju, si sunmọ etile. 5 Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ? 6 O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe. 7 Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ. 8 Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe, 9 Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi? 10 Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye. 11 Jesu si mu iṣu akara wọnni; nigbati o si ti dupẹ, o pin wọn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si pín wọn fun awọn ti o joko; bẹ̃ gẹgẹ si li ẹja ni ìwọn bi nwọn ti nfẹ. 12 Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé. 13 Bẹ̃ni nwọn kó wọn jọ nwọn si fi ajẹkù ìṣu akara barle marun na kún agbọn mejila eyi ti o ṣikù, fun awọn ti o jẹun. 14 Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye. 15 Nigbati Jesu si woye pe, nwọn nfẹ wá ifi agbara mu on lọ ifi jọba, o tún pada lọ sori òke on nikan.

Jesu Rìn lórí Omi

16 Nigbati alẹ si lẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sinu okun. 17 Nwọn si bọ sinu ọkọ̀, nwọn si rekọja okun lọ si Kapernaumu. Okunkun si ti kùn, Jesu kò si ti ide ọdọ wọn. 18 Okun si nru nitori ẹfufu lile ti nfẹ. 19 Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn. 20 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. 21 Nitorina nwọn fi ayọ̀ gbà a sinu ọkọ̀: lojukanna ọkọ̀ na si de ilẹ ibiti nwọn gbé nlọ.

Àwọn Eniyan Wá Jesu Rí

22 Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ; 23 (Ṣugbọn awọn ọkọ̀ miran ti Tiberia wá, leti ibi ti nwọn gbe jẹ akara, lẹhin igbati Oluwa ti dupẹ:) 24 Nitorina nigbati awọn enia ri pe, Jesu kò si nibẹ̀, tabi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn pẹlu wọ̀ ọkọ̀ lọ si Kapernaumu, nwọn nwá Jesu.

Jesu ni Oúnjẹ Ìyè

25 Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi? 26 Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó. 27 Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí. 28 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun? 29 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́. 30 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? iṣẹ kini iwọ ṣe? 31 Awọn baba wa jẹ manna li aginjù; gẹgẹ bi a ti kọ o pe, O fi onjẹ fun wọn jẹ lati ọrun wá. 32 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá. 33 Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye. 34 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai. 35 Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai. 36 Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́. 37 Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri. 38 Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. 39 Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ. 40 Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. 41 Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá. 42 Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? etiṣe wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá? 43 Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin. 44 Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. 45 A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá. 46 Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba. 47 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun. 48 Emi li onjẹ ìye. 49 Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú. 50 Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú. 51 Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye. 52 Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ? 53 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin. 54 Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. 55 Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ. 56 Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀. 57 Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi. 58 Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai. 59 Nkan wọnyi li o sọ ninu sinagogu, bi o ti nkọni ni Kapernaumu.

Ọ̀rọ̀ Ìyè Ainipẹkun

60 Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ? 61 Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi? 62 Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́? 63 Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni. 64 Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn. 65 O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá. 66 Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si ba a rìn mọ́. 67 Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi? 68 Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun. 69 Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye. 70 Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin mejila kọ́ ni mo yàn, ọkan ninu nyin kò ha si yà Èṣu? 71 O nsọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni: nitoripe on li ẹniti yio fi i hàn, ọkan ninu awọn mejila.

Johanu 7

Àwọn Arakunrin Jesu kò gbà á gbọ́

1 LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a. 2 Ajọ awọn Ju ti iṣe ajọ ìpagọ́, sunmọ etile tan. 3 Nitorina awọn arakunrin rẹ̀ wi fun u pe, Lọ kuro nihinyi, ki o si lọ si Judea, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ pẹlu ki o le ri iṣẹ rẹ ti iwọ nṣe. 4 Nitoripe kò si ẹnikẹni ti iṣe ohunkohun nikọ̀kọ, ti on tikararẹ̀ si nfẹ ki a mọ̀ on ni gbangba. Bi iwọ ba nṣe nkan wọnyi, fi ara rẹ hàn fun araiye. 5 Nitoripe awọn arakunrin rẹ̀ kò tilẹ gbà a gbọ́. 6 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Akokò temi kò ti ide: ṣugbọn akokò ti nyin ni imura tan nigbagbogbo. 7 Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru. 8 Ẹnyin ẹ gòke lọ si ajọ yi: emi kì yio ti igoke lọ si ajọ yi; nitoriti akokò temi kò ti ide. 9 Nigbati o ti sọ nkan wọnyi fun wọn tan, o duro ni Galili sibẹ̀.

Jesu Lọ sí Àjọ̀dún Ìpàgọ́

10 Ṣugbọn nigbati awọn arakunrin rẹ̀ gòke lọ tan, nigbana li on si gòke lọ si ajọ na pẹlu, kì iṣe ni gbangba, ṣugbọn bi ẹnipe nikọ̀kọ. 11 Nigbana li awọn Ju si nwá a kiri nigba ajọ, wipe, Nibo li o wà? 12 Kikùn pipọ si wà larin awọn ijọ enia nitori rẹ̀: nitori awọn kan wipe, Enia rere ni iṣe: awọn miran wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn o ntàn enia jẹ ni. 13 Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju. 14 Nigbati ajọ de arin Jesu gòke lọ si tẹmpili o si nkọ́ni. 15 Ẹnu si yà awọn Ju, nwọn wipe, ọkunrin yi ti ṣe mọ̀ iwe, nigbati ko kọ́ ẹ̀kọ́? 16 Nitorina Jesu da wọn lohùn, o si wipe, Ẹkọ́ mi ki iṣe temi, bikoṣe ti ẹniti o rán mi. 17 Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi. 18 Ẹniti nsọ̀ ti ara rẹ̀ nwá ogo ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti nwá ogo ẹniti o rán a, on li olõtọ, kò si si aiṣododo ninu rẹ̀. 19 Mose kò ha fi ofin fun yin, kò si ẹnikẹni ninu nyin ti o pa ofin na mọ́? Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá ọ̀na lati pa mi? 20 Ijọ enia dahùn nwọn si wipe, Iwọ li ẹmi èṣu: tani nwá ọ̀na lati pa ọ? 21 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, kìki iṣẹ àmi kan ni mo ṣe, ẹnu si yà gbogbo nyin. 22 Nitori eyi ni Mose fi ìkọlà fun nyin (kì iṣe nitoriti iṣe ti Mose, ṣugbọn ti awọn baba); nitorina ẹ si nkọ enia ni ilà li ọjọ isimi. 23 Bi enia ba ngbà ikọla li ọjọ isimi, ki a ma bà rú ofin Mose, ẹ ha ti ṣe mbinu si mi, nitori mo mu enia kan larada ṣáṣa li ọjọ isimi? 24 Ẹ máṣe idajọ nipa ode ara, ṣugbọn ẹ mã ṣe idajọ ododo.

Àbí Jesu Ni Mesaia náà?

25 Nigbana li awọn kan ninu awọn ara Jerusalemu wipe, Ẹniti nwọn nwá ọ̀na ati pa kọ́ yi? 26 Si wo o, o nsọrọ ni gbangba, nwọn kò si wi nkankan si i. Awọn olori ha mọ̀ nitõtọ pe, eyi ni Kristi na? 27 Ṣugbọn awa mọ̀ ibi ti ọkunrin yi gbé ti wá: ṣugbọn nigbati Kristi ba de, kò si ẹniti yio mọ̀ ibiti o gbé ti wà. 28 Nigbana ni Jesu kigbe ni tẹmpili bi o ti nkọ́ni, wipe, Ẹnyin mọ̀ mi, ẹ si mọ̀ ibiti mo ti wá: emi ko si wá fun ara mi, ṣugbọn olõtọ li ẹniti o rán mi, ẹniti ẹnyin kò mọ̀. 29 Ṣugbọn emi mọ̀ ọ: nitoripe lọdọ rẹ̀ ni mo ti wá, on li o si rán mi. 30 Nitorina nwọn nwá ọ̀na ati mú u: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e, nitoriti wakati rẹ̀ kò ti ide. 31 Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe?

Wọ́n Rán Àwọn Oníṣẹ́ Lọ Mú Jesu

32 Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u. 33 Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi. 34 Ẹnyin yio wá mi, ẹnyin kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, enyin kì yio le wá. 35 Nitorina li awọn Ju mba ara wọn sọ pe, Nibo ni ọkunrin yi yio gbé lọ, ti awa kì yio fi ri i? yio ha lọ sarin awọn Hellene ti nwọn fọnká kiri, ki o si ma kọ́ awọn Hellene bi? 36 Ọrọ kili eyi ti o sọ yi, Ẹnyin ó wá mi, ẹ kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, ẹnyin kì yio le wá?

Odò Omi Ìyè

37 Lọjọ ikẹhìn, ti iṣe ọjọ nla ajọ, Jesu duro, o si kigbe, wipe, Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu. 38 Ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́, gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi, lati inu rẹ̀ ni odò omi ìye yio ti ma ṣàn jade wá. 39 (Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.)

Ìyapa Bẹ́ Sáàrin Àwọn Eniyan

40 Nitorina nigbati ọ̀pọ ninu ijọ enia gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na. 41 Awọn miran wipe, Eyi ni Kristi na. Ṣugbọn awọn kan wipe Kinla, Kristi yio ha ti Galili wá bi? 42 Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà? 43 Bẹ̃ni iyapa wà larin ijọ enia nitori rẹ̀. 44 Awọn miran ninu wọn si fé lati mu u; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e.

Àwọn Aláṣẹ Kò Gba Jesu Gbọ́

45 Nitorina awọn onṣẹ pada tọ̀ awọn olori alufa ati awọn Farisi wá; nwọn si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi mu u wá? 46 Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri. 47 Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi? 48 O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́? 49 Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu. 50 Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn), 51 Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi? 52 Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili ndan? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide. 53 Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.

Johanu 8

Ìtàn Obinrin tí Ó Ṣe Àgbèrè

1 JESU si lọ si ori òke Olifi. 2 O si tún pada wá si tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, gbogbo enia si wá sọdọ rẹ̀; o si joko, o nkọ́ wọn. 3 Awọn akọwe ati awọn Farisi si mu obinrin kan wá sọdọ rẹ̀, ti a mu ninu panṣaga; nigbati nwọn si mu u duro larin, 4 Nwọn wi fun u pe, Olukọni, a mu obinrin yi ninu panṣaga, ninu ṣiṣe e pãpã. 5 Njẹ ninu ofin, Mose paṣẹ fun wa lati sọ iru awọn bẹ̃ li okuta pa: ṣugbọn iwọ ha ti wi? 6 Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ. 7 Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u. 8 O si tún bẹ̀rẹ̀ silẹ, o nkọwe ni ilẹ. 9 Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà. 10 Jesu si gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun u pe, Obinrin yi, awọn dà? kò si ẹnikan ti o da ọ lẹbi? 11 O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹ̃li emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.

Jesu ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé

12 Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye. 13 Nitorina awọn Farisi wi fun u pe, Iwọ njẹri ara rẹ; ẹrí rẹ kì iṣe otitọ. 14 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Bi mo tilẹ njẹri fun ara mi, otitọ li ẹrí mi: nitoriti mo mọ̀ ibiti mo ti wá, mo si mọ̀ ibiti mo nlọ; ṣugbọn ẹnyin kò le mọ̀ ibiti mo ti wá, ati ibiti mo nlọ. 15 Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni. 16 Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi. 17 Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji. 18 Emi li ẹniti njẹri ara mi, ati Baba ti o rán mi si njẹri fun mi. 19 Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu. 20 Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.

Ta Ni Jesu?

21 Nitorina o tun wi fun wọn pe, Emi nlọ, ẹnyin yio si wá mi, ẹ ó si kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: ibiti emi gbe nlọ, ẹnyin kì ó le wá. 22 Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá. 23 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi. 24 Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin. 25 Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe. 26 Mo ni ohun pupọ̀ lati sọ, ati lati ṣe idajọ nipa nyin: ṣugbọn olõtọ li ẹniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbọ lati ọdọ rẹ̀ wá, nwọnyi li emi nsọ fun araiye. 27 Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn. 28 Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi. 29 Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo. 30 Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.

Òtítọ́ yóo sọ Yín di Òmìnira

31 Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ. 32 Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira. 33 Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira? 34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ. 35 Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai. 36 Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ. 37 Mo mọ̀ pe irú-ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe; ṣugbọn ẹ nwá ọ̀na ati pa mi, nitori ọ̀rọ mi kò ri àye ninu nyin. 38 Ohun ti emi ti ri lọdọ Baba ni mo nsọ: ẹnyin pẹlu si nṣe eyi ti ẹnyin ti gbọ lati ọdọ baba nyin. 39 Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣẹ Abrahamu. 40 Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nwá ọ̀na ati pa mi, ẹniti o sọ otitọ fun nyin, eyi ti mo ti gbọ́ lọdọ Ọlọrun: Abrahamu kò ṣe eyi. 41 Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun. 42 Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe Ọlọrun ni Baba nyin, ẹnyin iba fẹran mi: nitoriti emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wá: bẹ̃li emi kò si wá fun ara mi, ṣugbọn on li o rán mi. 43 Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni. 44 Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke. 45 Ṣugbọn nitori emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbà mi gbọ́. 46 Tani ninu nyin ti o ti idá mi li ẹbi ẹ̀ṣẹ? Bi mo ba nsọ otitọ ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà mi gbọ́? 47 Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.

Jesu ti wà ṣiwaju Abrahamu

48 Awọn Ju dahùn nwọn si wi fun u pe, Awa kò wi nitõtọ pe, ara Samaria ni iwọ iṣe, ati pe iwọ li ẹmi èṣu? 49 Jesu dahùn wipe, Emi kò li ẹmi èṣu; ṣugbọn emi mbọlá fun Baba mi, ẹnyin kò si bọla fun mi. 50 Emi kò wá ogo ara mi: ẹnikan mbẹ ti o nwà a ti o si nṣe idajọ. 51 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, ki yio ri ikú lailai. 52 Awọn Ju wi fun u pe, Nigbayi ni awa mọ̀ pe iwọ li ẹmi èṣu. Abrahamu kú, ati awọn woli; iwọ si wipe, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, kì yio tọ́ ikú wò lailai. 53 Iwọ ha pọ̀ju Abrahamu baba wa lọ, ẹniti o kú? awọn woli si kú: tani iwọ nfi ara rẹ pè? 54 Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe: 55 Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́. 56 Abrahamu baba nyin yọ̀ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ̀. 57 Nitorina awọn Ju wi fun u pe, Ọdún rẹ kò ti ito adọta, iwọ si ti ri Abrahamu? 58 Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà. 59 Nitorina nwọn gbé okuta lati sọ lù u: ṣugbọn Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, o si jade kuro ni tẹmpili.

Johanu 9

Jesu Wo Ẹni tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú Sàn

1 BI o si ti nkọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibí rẹ̀ wá. 2 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju? 3 Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀. 4 Emi kò le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ̀ wá nigbati ẹnikan kì o le ṣe iṣẹ. 5 Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye. 6 Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na, 7 O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran. 8 Njẹ awọn aladugbo ati awọn ti o ri i nigba atijọ pe alagbe ni iṣe, wipe, Ẹniti o ti njoko ṣagbe kọ́ yi? 9 Awọn kan wipe, On ni: awọn ẹlomiran wipe, Bẹ̃kọ, o jọ ọ ni: ṣugbọn on wipe, Emi ni. 10 Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là? 11 O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran. 12 Nwọn si wi fun u pe, On na ha dà? O wipe, emi kò mọ̀.

Àwọn Farisi Wádìí Ìwòsàn Afọ́jú Náà

13 Nwọn mu ẹniti oju rẹ̀ ti fọ́ ri wá sọdọ awọn Farisi. 14 Njẹ ọjọ isimi lọjọ na nigbati Jesu ṣe amọ̀ na, ti o si là a loju. 15 Nitorina awọn Farisi pẹlu tún bi i lẽre, bi o ti ṣe riran. O si wi fun wọn pe, O fi amọ̀ le oju mi, mo si wẹ̀ mo si riran. 16 Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn. 17 Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe. 18 Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju. 19 Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi? 20 Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju: 21 Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀. 22 Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu. 23 Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre. 24 Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe. 25 Nitorina o dahùn o si wipe, Bi ẹlẹṣẹ ni, emi kò mọ̀: ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi. 26 Nitorina nwọn wi fun u pe, Kili o ṣe si ọ? o ti ṣe là ọ loju? 27 O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi? 28 Nwọn si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si wipe, Iwọ li ọmọ-ẹhin rẹ̀; ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose li awa. 29 Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá. 30 Ọkunrin na dahùn o si wi fun wọn pe, Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju. 31 Awa mọ̀ pe, Ọlọrun ki igbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ̀, on ni igbọ́ tirẹ̀. 32 Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí. 33 Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun. 34 Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode. 35 Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi? 36 On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́? 37 Jesu wi fun u pe, Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi. 38 O si wipe, Oluwa, mo gbagbọ́, o si wolẹ fun u. 39 Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju. 40 Ninu awọn Farisi ti o wà lọdọ rẹ̀ gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si wi fun u pe, Awa pẹlu fọju bi? 41 Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.

Johanu 10

Jesu Fi Aguntan Ṣe Àkàwé

1 LÕTỌ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnu-ọ̀na wọ̀ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà. 2 Ṣugbọn ẹniti o ba ba ti ẹnu-ọ̀na wọle, on ni iṣe oluṣọ awọn agutan. 3 On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade. 4 Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀. 5 Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò. 6 Owe yi ni Jesu pa fun wọn: ṣugbọn òye ohun ti nkan wọnni jẹ ti o nsọ fun wọn kò yé wọn.

Jesu Ni Olùṣọ́-Aguntan Rere

7 Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan. 8 Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn. 9 Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko. 10 Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ. 11 Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan. 12 Ṣugbọn alagbaṣe, ti kì iṣe oluṣọ-agutan, ẹniti awọn agutan kì iṣe tirẹ̀, o ri ikõkò mbọ̀, o si fi awọn agutan silẹ, o si sá lọ: ikõkò si mu awọn agutan, o si fọn wọn ká kiri. 13 Alagbaṣe sá lọ nitoriti iṣe alagbaṣe, kò si náni awọn agutan. 14 Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi. 15 Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan. 16 Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan. 17 Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmí mi lelẹ, ki emi ki o le tún gbà a. 18 Ẹnikan kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn mo fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tún gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá. 19 Nitorina iyapa tun wà larin awọn Ju nitori ọ̀rọ wọnyi. 20 Ọpọ ninu wọn si wipe, O li ẹmi èṣu, ori rẹ̀ si bajẹ; ẽṣe ti ẹnyin ngbọ̀rọ rẹ̀? 21 Awọn miran wipe, Wọnyi kì iṣe ọ̀rọ ẹniti o li ẹmi èsu. Ẹmi èsu le là oju awọn afọju bi?

Àwọn Juu Kọ Jesu

22 O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni. 23 Jesu si nrìn ni tẹmpili, nì ìloro Solomoni. 24 Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba. 25 Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi. 26 Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ́, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin. 27 Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin: 28 Emi si fun wọn ni ìye ainipẹkun; nwọn kì o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ mi. 29 Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi. 30 Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi. 31 Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u. 32 Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta? 33 Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun. 34 Jesu da wọn lohùn pe, A kò ha ti kọ ọ ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe, ọlọrun li ẹnyin iṣe? 35 Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ, 36 Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi? 37 Bi emi kò ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbọ́. 38 Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gbà iṣẹ na gbọ́: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ̀. 39 Nwọn si tun nwá ọ̀na lati mu u: o si bọ́ lọwọ wọn. 40 O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko. 41 Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi. 42 Awọn enia pipọ nibẹ̀ si gbà a gbọ́.

Johanu 11

Ikú Lasaru

1 ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀. 2 (Maria na li ẹniti o fi ororo ikunra kùn Oluwa, ti o si fi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù, arakunrin rẹ̀ ni Lasaru iṣe, ara ẹniti kò dá.) 3 Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da. 4 Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀. 5 Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ̀, ati Lasaru. 6 Nitorina nigbati o ti gbọ́ pe, ara rẹ̀ kò da, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà. 7 Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea. 8 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀? 9 Jesu dahún pe, Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan? Bi ẹnikan ba rìn li ọsán, kì yio kọsẹ̀, nitoriti o ri imọlẹ aiye yi. 10 Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀. 11 Nkan wọnyi li o sọ: lẹhin eyini o si wi fun wọn pe, Lasaru ọrẹ́ wa sùn; ṣugbọn emi nlọ ki emi ki o le jí i dide ninu orun rẹ̀. 12 Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn. 13 Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun. 14 Nigbana ni Jesu wi fun wọn gbangba pe, Lasaru kú. 15 Emi si yọ̀ nitori nyin, ti emi kò si nibẹ̀, Ki ẹ le gbagbọ́; ṣugbọn ẹ jẹ ki a lọ sọdọ rẹ̀. 16 Nitorina Tomasi, ẹniti a npè ni Didimu, wi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu.

Jesu Ni Ajinde ati Ìyè

17 Nitorina nigbati Jesu de, o ri pe a ti tẹ́ ẹ sinu ibojì ni ijọ mẹrin na. 18 Njẹ Betani sunmọ Jerusalemu to furlongi mẹdogun: 19 Ọ̀pọ ninu awọn Ju si wá sọdọ Marta ati Maria, lati tù wọn ninu nitori ti arakunrin wọn. 20 Nitorina nigbati Marta gbọ́ pe Jesu mbọ̀ wá, o jade lọ ipade rẹ̀: ṣugbọn Maria joko ninu ile. 21 Nigbana ni Marta wi fun Jesu pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kì ba tí kú. 22 Ṣugbọn nisisiyi na, mo mọ̀ pe, ohunkohun ti iwọ ba bère lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun yio fifun ọ. 23 Jesu wi fun u pe, Arakunrin rẹ yio jinde. 24 Marta wi fun u pe, mo mọ̀ pe yio jinde li ajinde nigbẹhin ọjọ. 25 Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yio yè: 26 Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gbà mi gbọ́, kì yio kú lailai. Iwọ gbà eyi gbọ́? 27 O wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa: emi gbagbọ́ pe, iwọ ni Kristi na Ọmọ Ọlọrun, ẹniti mbọ̀ wá aiye.

Jesu Abánidárò

28 Nigbati o si ti wi eyi tan, o lọ, o si pè Maria arabinrin rẹ̀ sẹhin wipe, Olukọni de, o si npè ọ. 29 Nigbati o gbọ́, o dide lọgan, o si wá sọdọ rẹ̀. 30 Jesu kò sá ti iwọ̀ ilu, ṣugbọn o wà nibikanna ti Marta pade rẹ̀. 31 Nitorina awọn Ju ti o wà lọdọ rẹ̀ ninu ile, ti nwọn ntù u ninu, nigbati nwọn ri ti Maria dide kánkan, ti o si jade, nwọn tẹ̀le e, nwọn ṣebi o nlọ si ibojì lọ isọkun nibẹ̀. 32 Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú. 33 Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ, 34 O si wipe, Nibo li ẹnyin gbé tẹ́ ẹ si? Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, wá wò o. 35 Jesu sọkun. 36 Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to! 37 Awọn kan ninu wọn si wipe, Ọkunrin yi, ẹniti o là oju afọju, kò le ṣe ki ọkunrin yi má ku bi?

Lasaru Tún Di Alààyè

38 Nigbana ni Jesu tún kerora ninu ara rẹ̀, o wá si ibojì. O si jẹ ihò, a si gbé okuta le ẹnu rẹ̀. 39 Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú. 40 Jesu wi fun u pe, Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ́, iwọ o ri ogo Ọlọrun? 41 Nigbana ni nwọn gbé okuta na kuro nibiti a gbe tẹ́ okú na si. Jesu si gbé oju rẹ̀ soke, o si wipe, Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ́ ti emi. 42 Emi si ti mọ̀ pe, iwọ a ma gbọ́ ti emi nigbagbogbo: ṣugbọn nitori ijọ enia ti o duro yi ni mo ṣe wi i, ki nwọn ki o le gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. 43 Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o kigbe li ohùn rara pe, Lasaru, jade wá. 44 Ẹniti o kú na si jade wá, ti a fi aṣọ okú dì tọwọ tẹsẹ a si fi gèle dì i loju. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tú u, ẹ si jẹ ki o mã lọ.

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu

45 Nitorina li ọ̀pọ awọn Ju ti o wá sọdọ Maria, ti nwọn ri ohun ti Jesu ṣe, nwọn gbà a gbọ. 46 Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn tọ̀ awọn Farisi lọ, nwọn si sọ fun wọn ohun ti Jesu ṣe. 47 Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi. 48 Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ̃, gbogbo enia ni yio gbà a gbọ́: awọn ará Romu yio si wá gbà ilẹ ati orilẹ-ède wa pẹlu. 49 Ṣugbọn Kaiafa, ọkan ninu wọn, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na, o wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohunkohun rara. 50 Bẹ̃ni ẹ kò si ronu pe, o ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ède ki o má bà ṣegbé. 51 Ki iṣe fun ara rẹ̀ li o sọ eyi: ṣugbọn bi o ti jẹ olori alufa li ọdún na, o sọtẹlẹ pe, Jesu yio kú fun orilẹ-ède na: 52 Ki si iṣe kìki fun orilẹ-ède na nikan, ṣugbọn pẹlu ki o le kó awọn ọmọ Ọlọrun ti a ti funka kiri jọ li ọkanṣoṣo. 53 Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a. 54 Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 55 Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́. 56 Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ? 57 Njẹ awọn olori alufa ati awọn Farisi ti paṣẹ pe bi ẹnikan ba mọ̀ ibi ti o gbé wà, ki o fi i hàn, ki nwọn ki o le mu u.

Johanu 12

Maria Tú Òróró Dà Sára Jesu ní Bẹtani

1 NITORINA nigbati ajọ irekọja kù ijọ mẹfa, Jesu wá si Betani, nibiti Lasaru wà, ẹniti o ti kú, ti Jesu ji dide kuro ninu okú. 2 Nwọn si se ase-alẹ fun u nibẹ: Marta si nṣe iranṣẹ: ṣugbọn Lasaru jẹ ọkan ninu awọn ti o joko nibi tabili pẹlu rẹ̀. 3 Nigbana ni Maria mu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabùla, olowo iyebiye, o si nfi kùn Jesu li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù: ile si kún fun õrùn ikunra na. 4 Nigbana li ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni, ẹniti yio fi i hàn, wipe, 5 Ẽṣe ti a kò tà ororo ikunra yi ni ọ̃durun owo idẹ ki a si fifun awọn talakà? 6 Ṣugbọn o wi eyi, ki iṣe nitoriti o náni awọn talakà; ṣugbọn nitoriti iṣe olè, on li o si ni àpo, a si ma gbé ohun ti a fi sinu rẹ̀. 7 Nigbana ni Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀, o ṣe e silẹ dè ọjọ sisinku mi. 8 Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn emi li ẹ kò ni nigbagbogbo.

Ọ̀tẹ̀ láti Pa Lasaru

9 Nitorina ijọ enia ninu awọn Ju li o mọ̀ pe o wà nibẹ̀: nwọn si wá, kì iṣe nitori Jesu nikan, ṣugbọn ki nwọn le ri Lasaru pẹlu, ẹniti o ti jí dide kuro ninu okú. 10 Ṣugbọn awọn olori alufa gbìmọ ki nwọn le pa Lasaru pẹlu; 11 Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li ọ̀pọ ninu awọn Ju jade lọ, nwọn si gbà Jesu gbọ́.

Jesu Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ẹ̀yẹ

12 Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu, 13 Nwọn mu imọ̀-ọ̀pẹ, nwọn si jade lọ ipade rẹ̀, nwọn si nkigbe pe, Hosanna: Olubukun li ẹniti mbọ̀wá li orukọ Oluwa, Ọba Israeli. 14 Nigbati Jesu si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan, o gùn u; gẹgẹ bi a ti kọwe pe, 15 Má bẹ̀ru, ọmọbinrin Sioni: wo o, Ọba rẹ mbọ̀ wá, o joko lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. 16 Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si. 17 Nitorina ijọ enia ti o wà lọdọ rẹ̀, nigbati o pè Lasaru jade ninu iboji rẹ̀, ti o si jí i dide kuro ninu okú, nwọn jẹri. 18 Nitori eyi ni ijọ enia si ṣe lọ ipade rẹ̀, nitoriti nwọn gbọ́ pe o ti ṣe iṣẹ àmi yi. 19 Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.

Àwọn Hellene Fẹ́ Rí Jesu

20 Awọn Hellene kan si wà ninu awọn ti o gòke wá lati sìn nigba ajọ: 21 Awọn wọnyi li o tọ̀ Filippi wá, ẹniti iṣe ará Betsaida ti Galili, nwọn si mbère lọwọ rẹ̀, wipe, Alàgba, awa nfẹ ri Jesu. 22 Filippi wá, o si sọ fun Anderu; Anderu ati Filippi wá, nwọn si sọ fun Jesu. 23 Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo. 24 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe wóro alikama ba bọ́ si ilẹ̀, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọ̀pọlọpọ eso. 25 Ẹniti o ba fẹ ẹmí rẹ̀ yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si korira ẹmi rẹ̀ li aiye yi ni yio si pa a mọ́ titi fi di ìye ainipẹkun. 26 Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun.

A Níláti Gbé Ọmọ-Eniyan Sókè

27 Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi. 28 Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo. 29 Nitorina ijọ enia ti o duro nibẹ̀, ti nwọn si gbọ́ ọ, wipe, Ãrá nsán: awọn ẹlomiran wipe, Angẹli kan li o mba a sọrọ. 30 Jesu si dahùn wipe, Ki iṣe nitori mi li ohùn yi ṣe wá, bikoṣe nitori nyin. 31 Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade. 32 Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi. 33 Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú. 34 Nitorina awọn ijọ enia da a lohùn wipe, Awa gbọ́ ninu ofin pe, Kristi wà titi lailai: iwọ ha ṣe wipe, A kò le ṣaima gbé Ọmọ-enia soke? tani iṣe Ọmọ-enia yi? 35 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Nigba diẹ si i ni imọlẹ wà lãrin nyin. Ẹ mã rìn nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ki òkunkun máṣe ba le nyin: ẹniti o ba si nrìn li òkunkun kò mọ̀ ibiti on gbé nlọ. 36 Nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ẹ gbà imọlẹ gbọ́, ki ẹ le jẹ ọmọ imọlẹ. Nkan wọnyi ni Jesu sọ, o si jade lọ, o fi ara pamọ́ fun wọn.

Àwọn Juu Kò Gbàgbọ́

37 Ṣugbọn bi o ti ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ ami to bayi li oju wọn, nwọn kò gbà a gbọ́; 38 Ki ọ̀rọ woli Isaiah lè ṣẹ, eyiti o sọ pe, Oluwa, tali o gbà iwasu wa gbọ́? ati tali a si fi apá Oluwa hàn fun? 39 Nitori eyi ni nwọn kò fi le gbagbọ́, nitori Isaiah si tún sọ pe, 40 O ti fọ́ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada. 41 Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rẹ̀, o si sọ̀rọ rẹ̀. 42 Sibẹ ọ̀pọ ninu awọn olori gbà a gbọ́ pẹlu; ṣugbọn nitori awọn Farisi nwọn kò jẹwọ rẹ̀, ki a má bà yọ wọn kuro ninu sinagogu: 43 Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.

Ọ̀rọ̀ Jesu ń dá Eniyan Lẹ́jọ́

44 Jesu si kigbe o si wipe, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, emi kọ li o gbàgbọ́, ṣugbọn ẹniti o rán mi. 45 Ẹniti o ba si ri mi, o ri ẹniti o rán mi. 46 Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o máṣe wà li òkunkun. 47 Bi ẹnikẹni ba si gbọ́ ọ̀rọ mi, ti kò si pa wọn mọ, emi kì yio ṣe idajọ rẹ̀: nitoriti emi kò wá lati ṣe idajọ aiye, bikoṣe lati gbà aiye là. 48 Ẹniti o ba kọ̀ mi, ti kò si gbà ọ̀rọ mi, o ni ẹnikan ti nṣe idajọ rẹ̀: ọ̀rọ ti mo ti sọ, on na ni yio ṣe idajọ rẹ̀ ni igbẹhin ọjọ. 49 Nitori emi kò dá ọrọ sọ fun ara mi, ṣugbọn Baba ti o rán mi, on li o ti fun mi li aṣẹ, ohun ti emi o sọ, ati eyiti emi o wi. 50 Emi si mọ̀ pe ìye ainipẹkun li ofin rẹ̀: nitorina, ohun wọnni ti mo ba wi, gẹgẹ bi Baba ti sọ fun mi, bẹ̀ni mo wi.

Johanu 13

Jesu Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀

1 NJE ki ajọ irekọja ki o to de, nigbati Jesu mọ̀ pe wakati rẹ̀ de tan, ti on ó ti aiye yi kuro lọ sọdọ Baba, fifẹ ti o fẹ awọn tirẹ̀ ti o wà li aiye, o fẹ wọn titi de opin. 2 Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn; 3 Ti Jesu si ti mọ̀ pe Baba ti fi ohun gbogbo le on lọwọ, ati pe lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun; 4 O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure. 5 Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn. 6 Nigbana li o de ọdọ Simoni Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa, iwọ nwẹ̀ mi li ẹsẹ? 7 Jesu dahùn o si wi fun u pe, Ohun ti emi nṣe iwọ kò mọ̀ nisisiyi; ṣugbọn yio ye ọ nikẹhin. 8 Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi. 9 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu. 10 Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin. 11 Nitoriti o mọ̀ ẹniti yio fi on hàn; nitorina li o ṣe wipe, Kì iṣe gbogbo nyin li o mọ́. 12 Nitorina lẹhin ti o wẹ̀ ẹsẹ wọn tan, ti o si ti mu agbáda rẹ̀, ti o tún joko, o wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ohun ti mo ṣe si nyin? 13 Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ. 14 Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. 15 Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin. 16 Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ. 17 Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn. 18 Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi. 19 Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni. 20 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà ẹnikẹni ti mo rán, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi o gbà ẹniti o rán mi.

Jesu Sọ Ẹni Tí Yóo fi Òun Hàn fún Àwọn Ọ̀tá

21 Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. 22 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi. 23 Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn. 24 Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ. 25 Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe? 26 Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. 27 Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan. 28 Kò si si ẹnikan nibi tabili ti o mọ̀ idi ohun ti o ṣe sọ eyi fun u. 29 Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà. 30 Nigbati o si ti gbà òkele na tan, o jade lojukanna: oru si ni. 31 Nitorina nigbati o jade lọ tan, Jesu wipe, Nisisiyi li a yìn Ọmọ-enia logo, a si yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀. 32 Bi a ba yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀, Ọlọrun yio si yìn i logo ninu on tikararẹ̀, yio si yìn i logo nisisiyi. 33 Ẹnyin ọmọde, nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin. Ẹnyin ó wá mi: ati gẹgẹ bi mo ti wi fun awọn Ju pe, Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì o le wá; bẹ̃ni mo si wi fun nyin nisisiyi. 34 Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin. 35 Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóo Sẹ́ Òun

36 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, nibo ni iwọ nlọ? Jesu da a lohùn pe, Nibiti emi nlọ, iwọ ki ó le tọ̀ mi nisisiyi; ṣugbọn iwọ yio tọ̀ mi nikẹhin. 37 Peteru wi fun u pe, Oluwa, ẽṣe ti emi ko fi le tọ̀ ọ nisisiyi? emi o fi ẹmí mi lelẹ nitori rẹ. 38 Jesu da a lohùn wipe, Iwọ o ha fi ẹmí rẹ lelẹ nitori mi? Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Akukọ kì yio kọ, ki iwọ ki o to sẹ́ mi nigba mẹta.

Johanu 14

Jesu Ni Ọ̀nà Dé Ọ̀dọ̀ Baba

1 Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu. 2 Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. 3 Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu. 4 Ẹnyin si mọ̀ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ̀ ọ̀na na. 5 Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na? 6 Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi. 7 Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i. 8 Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba na hàn wa, o si to fun wa. 9 Jesu wi fun u pe, Bi akokò ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yi, iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ̀ Filippi? ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wipe, Fi Baba hàn wa? 10 Iwọ kò ha gbagbọ́ pe, Emi wà ninu Baba, ati pe Baba wà ninu mi? ọ̀rọ ti emi nsọ fun nyin, emi kò da a sọ; ṣugbọn Baba ti ngbé inu mi, on ni nṣe iṣẹ rẹ̀. 11 Ẹ gbà mi gbọ́ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bẹ̃, ẹ gbà mi gbọ́ nitori awọn iṣẹ na pãpã. 12 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba. 13 Ohunkohun ti ẹnyin ba si bère li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yìn Baba logo ninu Ọmọ. 14 Bi ẹnyin ba bère ohunkohun li orukọ mi, emi ó ṣe e.

Jesu Ṣèlérí pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóo Wá

15 Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́. 16 Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai, 17 Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin. 18 Emi kì o fi nyin silẹ li alaini baba: emi ó tọ̀ nyin wá. 19 Nigba diẹ si i, aiye ki ó si ri mi mọ́; ṣugbọn ẹnyin ó ri mi: nitoriti emi wà lãye, ẹnyin ó wà lãye pẹlu. 20 Li ọjọ na li ẹnyin o mọ̀ pe, emi wà ninu Baba mi, ati ẹnyin ninu mi, ati emi ninu nyin. 21 Ẹniti o ba li ofin mi, ti o ba si npa wọn mọ́, on li ẹniti ọ fẹràn mi: ẹniti o ba si fẹràn mi, a o fẹrán rẹ̀ lati ọdọ Baba mi wá, emi o si fẹràn rẹ̀, emi o si fi ara mi hàn fun u. 22 Judasi wi fun u pe, (kì iṣe Iskariotu) Oluwa, ẽhatiṣe ti iwọ ó fi ara rẹ hàn fun awa, ti kì yio si ṣe fun araiye? 23 Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀. 24 Ẹniti kò fẹràn mi ni ko pa ọ̀rọ mi mọ́: ọ̀rọ ti ẹnyin ngbọ́ kì si iṣe ti emi, ṣugbọn ti Baba ti o rán mi. 25 Nkan wọnyi li emi ti sọ fun nyin, nigbati mo mba nyin gbe. 26 Ṣugbọn Olutunu na, Ẹmí Mimọ́, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ́ nyin li ohun gbogbo, yio si rán nyin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun nyin. 27 Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin: kì iṣe gẹgẹ bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin. Ẹ máṣe jẹ ki okàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri. 28 Ẹnyin sá ti gbọ́ bi mo ti wi fun nyin pe, Emi nlọ, emi ó si tọ̀ nyin wá. Ibaṣepe ẹnyin fẹràn mi, ẹnyin iba yọ̀ nitori emi nlọ sọdọ Baba: nitori Baba mi tobi jù mi lọ. 29 Emi si ti sọ fun nyin nisisiyi ki o to ṣẹ, pe nigbati o ba ṣẹ, ki ẹ le gbagbọ́. 30 Emi kì o ba nyin sọ̀rọ pipọ: nitori aladé aiye yi wá, kò si ni nkankan lọdọ mi. 31 Ṣugbọn nitori ki aiye le mọ̀ pe emi fẹràn Baba; gẹgẹ bi Baba si ti fi aṣẹ fun mi, bẹ̃ni emi nṣe. Ẹ dide, ẹ jẹ ki a lọ kuro nihinyi.

Johanu 15

Jesu Ni Igi Àjàrà

1 EMI ni àjara tõtọ, Baba mi si ni oluṣọgba. 2 Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹka ti o ba si so eso, on a wẹ̀ ẹ mọ́, ki o le so eso si i. 3 Ẹnyin mọ́ nisisiyi nitori ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin. 4 Ẹ mã gbé inu mi, emi o si mã gbé inu nyin. Gẹgẹ bi ẹka kò ti le so eso fun ara rẹ̀, bikoṣepe o ba ngbé inu àjara, bẹ̃li ẹnyin, bikoṣepe ẹ ba ngbé inu mi. 5 Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan. 6 Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna. 7 Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin. 8 Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi. 9 Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹ̃li emi si fẹ nyin: ẹ duro ninu ifẹ mi. 10 Bi ẹnyin ba pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi; gẹgẹ bi emi ti pa ofin Baba mi mọ́, ti mo si duro ninu ifẹ rẹ̀. 11 Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ̀ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ̀ nyin ki o le kún. 12 Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin. 13 Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọrẹ́ rẹ̀. 14 Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin. 15 Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin. 16 Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin. 17 Nkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun nyin pe, ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin.

Ọmọ-Aráyé Yóo Kórìíra Yín

18 Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ̀ pe, o ti korira mi ṣaju nyin. 19 Ibaṣepe ẹnyin iṣe ti aiye, aiye iba fẹ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitoriti ẹnyin kì iṣe ti aiye, ṣugbọn emi ti yàn nyin kuro ninu aiye, nitori eyi li aiye ṣe korira nyin. 20 Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu. 21 Ṣugbọn gbogbo nkan wọnyi ni nwọn o ṣe si nyin, nitori orukọ mi, nitoriti nwọn kò mọ̀ ẹniti o rán mi. 22 Ibaṣepe emi kò ti wá ki n si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun ẹ̀ṣẹ wọn. 23 Ẹniti o ba korira mi, o korira Baba mi pẹlu. 24 Ibaṣepe emi kò ti ṣe iṣẹ wọnni larin wọn, ti ẹlomiran kò ṣe ri, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn ti ri, nwọn si korira ati emi ati Baba mi. 25 Ṣugbọn eyi ṣe ki ọ̀rọ ti a kọ ninu ofin wọn ki o le ṣẹ pe, Nwọn korira mi li ainidi. 26 Ṣugbọn nigbati Olutunu na ba de, ẹniti emi ó rán si nyin lati ọdọ Baba wá, ani Ẹmi otitọ nì, ti nti ọdọ Baba wá, on na ni yio jẹri mi: 27 Ẹnyin pẹlu yio si jẹri mi, nitoriti ẹnyin ti wà pẹlu mi lati ipilẹṣẹ wá.

Johanu 16

1 NKAN wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki a má ba mu nyin kọsẹ̀. 2 Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun. 3 Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi. 4 Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.

Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́

5 Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ? 6 Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin. 7 Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; Anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin. 8 Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ: 9 Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́; 10 Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́; 11 Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi. 12 Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi. 13 Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin. 14 On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin. 15 Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.

Ìbànújẹ́ Yóo Di Ayọ̀

16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba. 17 Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba? 18 Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi. 19 Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi? 20 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ̀: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ̀. 21 Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye. 22 Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin. 23 Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin. 24 Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.

Jesu Ti Ṣẹgun Ayé

25 Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba. 26 Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin: 27 Nitoriti Baba tikararẹ̀ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá. 28 Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba. 29 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe. 30 Nigbayi li awa mọ̀ pe, iwọ mọ̀ ohun gbogbo, iwọ kò ni ki a bi ọ lẽre: nipa eyi li awa gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wá. 31 Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin gbagbọ́ wayi? 32 Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi. 33 Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.

Johanu 17

Adura Jesu

1 NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu: 2 Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u. 3 Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán. 4 Emi ti yìn ọ logo li aiye: emi ti parí iṣẹ ti iwọ fifun mi lati ṣe. 5 Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà. 6 Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. 7 Nisisiyi nwọn mọ̀ pe, ohunkohun gbogbo ti iwọ ti fifun mi, lati ọdọ rẹ wá ni. 8 Nitori ọ̀rọ ti iwọ fifun mi, emi ti fifun wọn, nwọn si ti gbà a, nwọn si ti mọ̀ nitõtọ pe, lọdọ rẹ ni mo ti jade wá, nwọn si gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. 9 Emi ngbadura fun wọn: emi kò gbadura fun araiye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi; nitoripe tirẹ ni nwọn iṣe. 10 Tirẹ sá ni gbogbo ohun ti iṣe temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti iṣe tirẹ; a si ti ṣe mi logo ninu wọn. 11 Emi kò si si li aiye mọ́, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ. Baba mimọ́, pa awọn ti o ti fifun mi mọ́, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, ani gẹgẹ bi awa. 12 Nigbati mo wà pẹlu wọn li aiye, mo pa wọn mọ li orukọ rẹ: awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pamọ́, ẹnikan ninu wọn kò si ṣègbe bikoṣe ọmọ egbé; ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ. 13 Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn. 14 Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye. 15 Emi ko gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi. 16 Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye. 17 Sọ wọn di mimọ́ ninu otitọ: otitọ li ọ̀rọ rẹ. 18 Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bẹ̃ li emi si rán wọn si aiye pẹlu. 19 Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ. 20 Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn; 21 Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi. 22 Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan; 23 Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pé li ọ̀kan; ki aiye ki o le mọ̀ pe, iwọ li o rán mi, ati pe iwọ si fẹràn wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹràn mi. 24 Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mã wò ogo mi, ti iwọ ti fi fifun mi: nitori iwọ sá fẹràn mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aiye. 25 Baba olododo, aiye kò mọ̀ ọ: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, awọn wọnyi si mọ̀ pe iwọ li o rán mi. 26 Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, emi ó si sọ ọ di mimọ̀: ki ifẹ ti iwọ fẹràn mi, le mã wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.

Johanu 18

Àwọn Ọ̀tá Mú Jesu

1 NIGBATI Jesu si ti sọ nkan wọnyi tan, o jade pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ soke odò Kedroni, nibiti agbala kan wà, ninu eyi ti o wọ̀, on ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 2 Judasi, ẹniti o fi i hàn, si mọ̀ ibẹ̀ pẹlu: nitori nigba-pupọ ni Jesu ima lọ sibẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. 3 Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà. 4 Nitorina bi Jesu ti mọ̀ ohun gbogbo ti mbọ̀ wá ba on, o jade lọ, o si wi fun wọn pe, Tali ẹ nwá? 5 Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn. 6 Nitorina bi o ti wi fun wọn pe, Emi niyi, nwọn bi sẹhin, nwọn si ṣubu lulẹ. 7 Nitorina o tún bi wọn lẽre, wipe, Tali ẹ nwá? Nwọn si wipe, Jesu ti Nasareti. 8 Jesu dahùn pe, Mo ti wi fun nyin pe, emi niyi: njẹ bi emi li ẹ ba nwá, ẹ jẹ ki awọn wọnyi mã lọ: 9 Ki ọ̀rọ nì ki o le ṣẹ, eyi ti o wipe, Awọn ti iwọ fifun mi, emi kò sọ ọ̀kan nù ninu wọn. 10 Nigbana ni Simoni Peteru ẹniti o ni idà, o fà a yọ, o si ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtun rẹ̀ sọnù. Orukọ iranṣẹ na ama jẹ Malku. 11 Nitorina Jesu wi fun Peteru pe, Tẹ̀ idà rẹ bọ inu àkọ rẹ̀: ago ti Baba ti fifun mi, emi ó ṣe alaimu u bi?

Wọ́n mú Jesu lọ siwaju Anna

12 Nigbana li ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati olori ẹṣọ́, ati awọn onṣẹ awọn Ju mu Jesu, nwọn si dè e. 13 Nwọn kọ́ fa a lọ sọdọ Anna; nitori on ni iṣe ana Kaiafa, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na. 14 Kaiafa sá ni iṣe, ẹniti o ti ba awọn Ju gbìmọ̀ pe, o ṣanfani ki enia kan kú fun awọn enia.

Peteru sẹ́ Jesu

15 Simoni Peteru si ntọ̀ Jesu lẹhin, ati ọmọ-ẹhin miran kan: ọmọ-ẹhin na jẹ ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o si ba Jesu wọ̀ afin olori alufa lọ. 16 Ṣugbọn Peteru duro li ẹnu-ọ̀na lode. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran nì, ti iṣe ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o jade lọ, o si ba oluṣọna na sọ ọ, o si mu Peteru wọle. 17 Nigbana li ọmọbinrin na ti nṣọ ẹnu-ọ̀na wi fun Peteru pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ọkunrin yi bi? O wipe, Emi kọ́. 18 Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.

Anna Bi Jesu nípa Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

19 Nigbana li olori alufa bi Jesu lẽre niti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati niti ẹkọ́ rẹ̀. 20 Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ. 21 Ẽṣe ti iwọ fi mbi mi lẽre? bere lọwọ awọn ti o ti gbọ́ ọ̀rọ mi, ohun ti mo wi fun wọn: wo o, awọn wọnyi mọ̀ ohun ti emi wi. 22 Bi o si ti wi eyi tan, ọkan ninu awọn onṣẹ ti o duro tì i fi ọwọ́ rẹ̀ lù Jesu, wipe, Olori alufa ni iwọ nda lohùn bẹ̃? 23 Jesu da a lohùn wipe, Bi mo ba sọrọ buburu, jẹri si buburu na: ṣugbọn bi rere ba ni, ẽṣe ti iwọ fi nlù mi? 24 Nitori Anna rán a lọ ni didè sọdọ Kaiafa olori alufa.

Peteru tún sẹ́ Jesu

25 Ṣugbọn Simoni Peteru duro, o si nyána. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? O si sẹ́, o si wipe, Emi kọ́. 26 Ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ olori alufa, ti iṣe ibatan ẹniti Peteru ke etí rẹ̀ sọnù, wipe, Emi kò ha ri ọ pẹlu rẹ̀ li agbala? 27 Nitorina Peteru tún sẹ́: lojukanna akukọ si kọ.

Wọ́n mú Jesu lọ siwaju Pilatu

28 Nitorina nwọn fa Jesu lati ọdọ Kaiafa lọ si ibi gbọ̀ngan idajọ: o si jẹ kùtukùtu owurọ̀; awọn tikarawọn kò wọ̀ ini gbọ̀ngàn idajọ, ki nwọn ki o má ṣe di alaimọ́, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ àse irekọja. 29 Nitorina Pilatu jade tọ̀ wọn lọ, o si wipe, Ẹ̀sun kili ẹnyin mu wá si ọkunrin yi? 30 Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ibamaṣepe ọkunrin yi nhùwa ibi, a kì ba ti fà a le ọ lọwọ. 31 Nitorina Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u tikaranyin, ki ẹ si ṣe idajọ rẹ̀ gẹgẹ bi ofin nyin. Nitorina li awọn Ju wi fun u pe, Kò tọ́ fun wa lati pa ẹnikẹni: 32 Ki ọ̀rọ Jesu ki o le ba ṣẹ, eyiti o sọ, ti o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú. 33 Nitorina Pilatu tún wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si pè Jesu, o si wi fun u pe, Ọba awọn Ju ni iwọ iṣe? 34 Jesu dahùn pe, Iwọ sọ eyi fun ara rẹ ni, tabi awọn ẹlomiran sọ ọ fun ọ nitori mi? 35 Pilatu dahùn wipe, Emi iṣe Ju bi? Awọn orilẹ-ède rẹ, ati awọn olori alufa li o fà ọ le emi lọwọ: kini iwọ ṣe? 36 Jesu dahùn wipe, Ijọba mi kì iṣe ti aiye yi: ibaṣepe ijọba mi iṣe ti aiye yi, awọn onṣẹ mi iba jà, ki a má bà fi mi le awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisisiyi ijọba mi kì iṣe lati ihin lọ. 37 Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi. 38 Pilatu wi fun u pe, Kili otitọ? Nigbati o si ti wi eyi tan, o tún jade tọ̀ awọn Ju lọ, o si wi fun wọn pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.

Wọ́n dá Jesu lẹ́bi Ikú

39 Ṣugbọn ẹnyin ni àṣa kan pe, ki emi ki o da ọkan silẹ fun nyin nigba ajọ irekọja: nitorina ẹ ha fẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin bi? 40 Nitorina gbogbo wọn tún kigbe wipe, Kì iṣe ọkunrin yi, bikoṣe Barabba. Ọlọṣa si ni Barabba.

Johanu 19

1 NITORINA ni Pilatu mu Jesu, o si nà a. 2 Awọn ọmọ-ogun si hun ade ẹgún, nwọn si fi de e li ori, nwọn si fi aṣọ igunwà elesè àluko wọ̀ ọ. 3 Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju. 4 Pilatu si tún jade, o si wi fun wọn pe, Wo o, mo mu u jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. 5 Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na! 6 Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀. 7 Awọn Ju da a lohùn wipe, Awa li ofin kan, ati gẹgẹ bi ofin wa o yẹ lati kú, nitoriti o fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun. 8 Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ yi ẹ̀ru tubọ ba a. 9 O si tun wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwọ ti wá? Ṣugbọn Jesu kò da a lohùn. 10 Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu? 11 Jesu da a lohun pe, Iwọ kì ba ti li agbara kan lori mi, bikoṣepe a fi i fun ọ lati oke wá: nitorina ẹniti o fi mi le ọ lọwọ li o ni ẹ̀ṣẹ pọ̀ju. 12 Nitori eyi Pilatu nwá ọ̀na lati dá a silẹ: ṣugbọn awọn Ju kigbe, wipe, Bi iwọ ba dá ọkunrin yi silẹ, iwọ kì iṣe ọrẹ́ Kesari: ẹnikẹni ti o ba ṣe ara rẹ̀ li ọba, o sọ̀rọ òdi si Kesari. 13 Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o mu Jesu jade wá, o si joko lori itẹ́ idajọ ti a npè ni Okuta-titẹ, ṣugbọn li ede Heberu, Gabbata. 14 O jẹ Ipalẹmọ́ ajọ irekọja, o jẹ iwọn wakati ẹkẹfa: o si wi fun awọn Ju pe, Ẹ wò Ọba nyin! 15 Nitorina nwọn kigbe wipe, Mu u kuro, mu u kuro, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Emi o ha kàn Ọba nyin mọ agbelebu bi? Awọn olori alufa dahùn wipe, 16 Awa kò li ọba bikoṣe Kesari. Nigbana li o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.

Wọ́n Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

17 Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota: 18 Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin. 19 Pilatu si kọ iwe akọle kan pẹlu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun ti a si kọ ni, JESU TI NASARETI ỌBA AWỌN JU. 20 Nitorina ọpọ awọn Ju li o kà iwe akọle yi: nitori ibi ti a gbé kàn Jesu mọ agbelebu sunmọ eti ilu: a si kọ ọ li ède Heberu, ati ti Latini, ati ti Helene. 21 Nitorina awọn olori alufa awọn Ju wi fun Pilatu pe, Máṣe kọ ọ pe, Ọba awọn Ju; ṣugbọn pe on wipe, Emi li Ọba awọn Ju. 22 Pilatu dahùn pe, Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ na. 23 Nigbana li awọn ọmọ-ogun, nigbati nwọn kàn jesu mọ agbelebu tan, nwọn mu aṣọ rẹ̀, nwọn si pín wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ-ogun kọkan, ati àwọtẹlẹ rẹ̀: ṣugbọn àwọ̀tẹlẹ na kò li ojuran, nwọn hun u lati oke titi jalẹ. 24 Nitorina nwọn wi fun ara wọn pe, Ẹ má jẹ ki a fà a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ kèké nitori rẹ̀, ti ẹniti yio jẹ: ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, Nwọn pín aṣọ mi larin ara wọn, nwọn si ṣẹ kèké fun aṣọ ileke mi. Nkan wọnyi li awọn ọmọ-ogun ṣe. 25 Iya Jesu ati arabinrin iya rẹ̀ Maria aya Klopa, ati Maria Magdalene, si duro nibi agbelebu. 26 Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! 27 Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀.

Ikú Jesu

28 Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi. 29 A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu. 30 Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.

Ọmọ-ogun Kan Fi Ọ̀kọ̀ Gún Jesu Lẹ́gbẹ̀ẹ́

31 Nitori o jẹ ọjọ Ipalẹmọ, ki okú wọn ma bà wà lori agbelebu li ọjọ isimi, (nitori ojọ nla ni ọjọ isimi na) nitorina awọn Ju bẹ̀ Pilatu pe ki a ṣẹ egungun itan wọn, ki a si gbe wọn kuro. 32 Nitorina awọn ọmọ-ogun wá, nwọn si ṣẹ́ egungun itan ti ekini, ati ti ekeji, ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀. 33 Ṣugbọn nigbati nwọn de ọdọ Jesu, ti nwọn si ri pe, o ti kú na, nwọn kò si ṣẹ́ egungun itan rẹ̀: 34 Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọ̀kọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna ẹ̀jẹ ati omi si tú jade. 35 Ẹniti o ri i si jẹri, otitọ si li ẹrí rẹ̀: o si mọ̀ pe õtọ li on wi, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́. 36 Nkan wọnyi ṣe, ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, A kì yio fọ́ egungun rẹ̀. 37 Iwe-mimọ́ miran ẹ̀wẹ si wipe, Nwọn o ma wò ẹniti a gún li ọ̀kọ.

Ìsìnkú Jesu

38 Lẹhin nkan wọnyi ni Josefu ará Arimatea, ẹniti iṣe ọmọ-ẹhin Jesu, ṣugbọn ni ikọ̀kọ nitori ìbẹru awọn Ju, o bẹ̀ Pilatu ki on ki o le gbé okú Jesu kuro: Pilatu si fun u li aṣẹ. Nitorina li o wá, o si gbé okú Jesu lọ. 39 Nikodemu pẹlu si wá, ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru lakọṣe, o si mu àdapọ̀ ojia ati aloe wá, o to ìwọn ọgọrun litra. 40 Bẹni nwọn gbé okú Jesu, nwọn si fi aṣọ ọ̀gbọ dì i pẹlu turari, gẹgẹ bi iṣe awọn Ju ti ri ni isinkú wọn. 41 Agbala kan si wà nibiti a gbé kàn a mọ agbelebu; ibojì titun kan sí wà ninu agbala na, ninu eyiti a ko ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. 42 Njẹ nibẹ ni nwọn si tẹ́ Jesu si, nitori Ipalẹmọ́ awọn Ju; nitori ibojì na wà nitosi.

Johanu 20

Ajinde Jesu

1 LI ọjọ ikini ọ̀sẹ ni kùtùkùtù nigbati ilẹ kò ti imọ́, ni Maria Magdalene wá si ibojì, o si ri pe, a ti gbé okuta kuro li ẹnu ibojì. 2 Nitorina o sare, o si tọ̀ Simoni Peteru wá, ati ọmọ-ẹhin miran na ẹniti Jesu fẹran, o si wi fun wọn pe, Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu ibojì, awa kò si mọ̀ ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. 3 Nigbana ni Peteru jade, ati ọmọ-ẹhin miran na, nwọn si wá si ibojì. 4 Awọn mejeji si jùmọ sare: eyi ọmọ-ẹhin miran nì si sare yà Peteru, o si tètekọ de ibojì. 5 O si bẹ̀rẹ, o si wò inu rẹ̀, o ri aṣọ ọgbọ na lelẹ; ṣugbọn on kò wọ̀ inu rẹ̀. 6 Nigbana ni Simoni Peteru ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀ de, o si wọ̀ inu ibojì, o si ri aṣọ ọ̀gbọ na wà nilẹ̀. 7 Ati pe gèle, ti o wà nibi ori rẹ̀, kò si wà pẹlu aṣọ ọgbọ na, ṣugbọn a ká a jọ ni ibikan fun ara rẹ̀. 8 Nigbana li ọmọ-ẹhin miran na, ẹniti o kọ de ibojì, wọ̀ inu rẹ̀ pẹlu, o si ri, o si gbagbọ́. 9 Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú. 10 Bẹli awọn ọmọ-ẹhin na si tun pada lọ si ile wọn.

Jesu Fara Han Maria Magidaleni

11 Ṣugbọn Maria duro leti ibojì lode, o nsọkun: bi o ti nsọkun, bẹli o bẹ̀rẹ, o si wò inu ibojì. 12 O si kiyesi awọn angẹli meji alaṣọ funfun, nwọn joko, ọkan niha ori, ati ọkan niha ẹsẹ̀, nibiti oku Jesu gbé ti sùn si. 13 Nwọn si wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? O si wi fun wọn pe, Nitoriti nwọn ti gbé Oluwa mi, emi kò si mọ̀ ibiti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. 14 Nigbati o si ti wi eyi tan, o yipada, o si ri Jesu duro, kò si mọ̀ pe Jesu ni. 15 Jesu wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? tani iwọ nwá? On ṣebi oluṣọgba ni iṣe, o wi fun u pe, Alàgba, bi iwọ ba ti gbé e kuro nihin, sọ ibiti o gbé tẹ ẹ si fun mi, emi o si gbé e kuro. 16 Jesu wi fun u pe, Maria. O si yipada, o wi fun u pe, Rabboni; eyi ti o jẹ Olukọni. 17 Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin. 18 Maria Magdalene wá, o si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe, on ti ri Oluwa, ati pe, o si ti sọ nkan wọnyi fun on.

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn

19 Lọjọ kanna, lọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati alẹ́ lẹ́, ti a si ti tì ilẹkun ibiti awọn ọmọ-ẹhin gbé pejọ, nitori ìbẹru awọn Ju, bẹni Jesu de, o duro larin, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin. 20 Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o fi ọwọ́ ati ìha rẹ̀ hàn wọn. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin yọ̀, nigbati nwọn ri Oluwa. 21 Nitorina Jesu si tún wi fun wọn pe, Alafia fun nyin: gẹgẹ bi Baba ti rán mi, bẹ̃li emi si rán nyin. 22 Nigbati o si ti wi eyi tan, o mí si wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà Ẹmí Mimọ́: 23 Ẹṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba fi jì, a fi ji wọn; ẹ̀ṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba da duro, a da wọn duro.

Tomasi Kò Kọ́kọ́ Gbàgbọ́

24 Ṣugbọn Tomasi, ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Didimu, kò wà pẹlu wọn nigbati Jesu de. 25 Nitorina awọn ọmọ-ẹhin iyokù wi fun u pe, Awa ti ri Oluwa. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣo li ọwọ́ rẹ̀ ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ́ mi si ìha rẹ̀, emi kì yio gbagbó. 26 Lẹhin ijọ mẹjọ awọn ọmọ-ẹhin si tún wà ninu ile, ati Tomasi pẹlu wọn: nigbati a si ti tì ilẹkun, Jesu de, o si duro larin, o si wipe, Alafia fun nyin. 27 Nigbana li o wi fun Tomasi pe, Mu ika rẹ wá nihin, ki o si wò ọwọ́ mi; si mu ọwọ́ rẹ wá nihin, ki o si fi si ìha mi: kì iwọ ki o máṣe alaigbagbọ́ mọ́, ṣugbọn jẹ onigbagbọ. 28 Tomasi dahun o si wi fun u pe, Oluwa mi ati Ọlọrun mi! 29 Jesu wi fun u pe, nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ́: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ́.

Èrèdí Ìwé Ìyìn Rere yìí

30 Ọpọlọpọ iṣẹ àmi miran ni Jesu ṣe niwaju awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ti a kò kọ sinu iwe yi: 31 Ṣugbọn wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun; ati ni gbigbàgbọ́, ki ẹnyin ki o le ni ìye li orukọ rẹ̀.

Johanu 21

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Meje

1 LẸHIN nkan wọnyi, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leti okun Tiberia; bayi li o si farahàn. 2 Simoni Peteru, ati Tomasi ti a npè ni Didimu, ati Natanaeli ara Kana ti Galili, ati awọn ọmọ Sebede, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji miran jùmọ wà pọ̀. 3 Simoni Peteru wi fun wọn pe, Emi nlọ ipẹja. Nwọn wi fun u pe, Awa pẹlu mba ọ lọ. Nwọn jade, nwọn si wọ̀ inú ọkọ̀; li oru na nwọn kò si mú ohunkohun. 4 Ṣugbọn nigbati ilẹ bẹrẹ si imọ́, Jesu duro leti okun: ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin kò mọ̀ pe Jesu ni. 5 Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọde, ẹ li onjẹ diẹ bi? Nwọn da a lohùn wipe, Rára o. 6 O si wi fun wọn pe, Ẹ sọ àwọn si apa ọtùn ọkọ̀, ẹnyin ó si ri. Nitorina nwọn sọ ọ, nwọn kò si le fà a jade nitori ọpọ ẹja. 7 Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun. 8 Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin iyoku mu ọkọ̀ kekere kan wá (nitoriti nwọn kò jina silẹ, ṣugbọn bi iwọn igba igbọnwọ); nwọn nwọ́ àwọn na ti o kún fun ẹja. 9 Nigbati nwọn gúnlẹ, nwọn ri iná ẹyín nibẹ, ati ẹja lori rẹ̀, ati akara. 10 Jesu wi fun wọn pe, Ẹ mú ninu ẹja ti ẹ pa nisisiyi wá. 11 Nitorina Simoni Peteru gòke, o si fà àwọn na wálẹ, o kún fun ẹja nla, o jẹ mẹtalelãdọjọ: bi nwọn si ti pọ̀ to nì, àwọn na kò ya. 12 Jesu wi fun wọn pe, Ẹ wá jẹun owurọ̀. Kò si si ẹnikan ninu awọn ọmọ-ẹhin ti o jẹ bi i pe, Tani iwọ iṣe? nitoriti nwọn mọ̀ pe Oluwa ni. 13 Jesu wá, o si mu akara, o si fifun wọn, gẹgẹ bẹ̃ si li ẹja. 14 Eyi ni igba kẹta nisisiyi ti Jesu farahàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.

Jesu ati Peteru

15 Njẹ lẹhin igbati nwọn jẹun owurọ̀ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn ọdọ-agutan mi. 16 O tún wi fun u nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi. 17 O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi. 18 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, nigbati iwọ wà li ọdọmọde, iwọ a ma di ara rẹ li àmurè, iwọ a si ma rìn lọ si ibiti iwọ ba fẹ: ṣugbọn nigbati iwọ ba di arugbo, iwọ o nà ọwọ́ rẹ jade, ẹlomiran yio si di ọ li amure, yio si mu ọ lọ si ibiti iwọ kò fẹ. 19 O wi eyi, o fi nṣapẹrẹ irú ikú ti yio fi yìn Ọlọrun logo. Lẹhin igbati o si ti wi eyi tan, o wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin.

Jesu ati Ọmọ-Ẹ̀hìn Tí Ó Fẹ́ràn

20 Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti o fi ọ hàn? 21 Nigbati Peteru ri i, o wi fun Jesu pe, Oluwa, Eleyi ha nkọ́? 22 Jesu wi fun u pe, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyini si ọ? iwọ mã tọ̀ mi lẹhin. 23 Nitorina ọ̀rọ yi si tàn ka lãrin awọn arakunrin pe, ọmọ-ẹhin nì kì yio kú: ṣugbọn Jesu kò wi fun u pe, On kì yio kú; ṣugbọn, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyinì si ọ? 24 Eyi li ọmọ-ẹhin na, ti o jẹri nkan wọnyi, ti o si kọwe nkan wọnyi: awa si mọ̀ pe, otitọ ni èrí rẹ̀.

Ìparí Ọ̀rọ̀

25 Ọpọlọpọ ohun miran pẹlu ni Jesu ṣe, eyiti bi a ba kọwe wọn li ọkọ̃kan, mo rò pe aiye pãpã kò le gbà iwe na ti a ba kọ. Amin.

Iṣe 1

Jesu Ṣe Ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́

1 TEOFILU, ìhìn iṣaju ni mo ti rò, niti ohun gbogbo ti Jesu bẹ̀rẹ si iṣe, ati si ikọ́, 2 Titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke, lẹhin ti o ti ti ipa Ẹmi Mimọ́ paṣẹ fun awọn aposteli ti o yàn: 3 Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun: 4 Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi: 5 Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.

Jesu Gòkè Re Ọ̀run

6 Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi? 7 O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀. 8 Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye. 9 Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn. 10 Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn; 11 Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.

A Yan Ẹlòmíràn Dípò Judasi

12 Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan. 13 Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà. 14 Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu. 15 Ni ijọ wọnni ni Peteru si dide duro li awujọ awọn ọmọ-ẹhin (iye awọn enia gbogbo ninu ijọ jẹ ọgọfa,) o ni, 16 Ẹnyin ará, Iwe-mimọ́ kò le ṣe ki o má ṣẹ, ti Ẹmi Mimọ́ ti sọtẹlẹ lati ẹnu Dafidi niti Judasi, ti o ṣe amọ̀na fun awọn ti o mu Jesu. 17 Nitori a kà a kún wa, o si ni ipin ninu iṣẹ iranṣẹ yi. 18 Njẹ ọkunrin yi sá ti fi ere aiṣõtọ rà ilẹ kan; nigbati o si ṣubu li ògedengbé, o bẹ́ li agbedemeji, gbogbo ifun rẹ̀ si tú jade. 19 O si di mimọ̀ fun gbogbo awọn ti ngbe Jerusalemu; nitorina li a fi npè igbẹ́ na ni Akeldama li ède wọn, eyini ni, Igbẹ́ ẹ̀jẹ. 20 A sá kọ ọ ninu Iwe Psalmu pe, Jẹ ki ibujoko rẹ̀ ki o di ahoro, ki ẹnikan ki o má si ṣe gbé inu rẹ̀, ati oyè rẹ̀, ni ki ẹlomiran gbà. 21 Nitorina ninu awọn ọkunrin wọnyi ti nwọn ti mba wa rìn ni gbogbo akoko ti Jesu Oluwa nwọle, ti o si njade lãrin wa, 22 Bẹ̀rẹ lati igba baptismu Johanu wá, titi o fi di ọjọ na ti a gbé e lọ soke kuro lọdọ wa, o yẹ ki ọkan ninu awọn wọnyi ṣe ẹlẹri ajinde rẹ̀ pẹlu wa. 23 Nwọn si yàn awọn meji, Josefu ti a npè ni Barsabba, ẹniti a sọ apele rẹ̀ ni Justu, ati Mattia. 24 Nwọn si gbadura, nwọn si wipe, Iwọ, Oluwa, olumọ̀ ọkàn gbogbo enia, fihàn ninu awọn meji yi, ewo ni iwọ yàn, 25 Ki o le gbà ipò ninu iṣẹ iranṣẹ yi ati iṣẹ aposteli, eyiti Judasi ṣubu kuro ninu rẹ̀ ki o le lọ si ipò ti ara rẹ̀. 26 Nwọn si dìbo fun wọn; ìbo si mu Mattia; a si kà a mọ awọn aposteli mọkanla.

Iṣe 2

Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ti Ṣe Dé

1 NIGBATI ọjọ Pentekosti si de, gbogbo nwọn fi ọkàn kan wà nibikan. 2 Lojijì iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹ̀fũfu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé joko. 3 Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rẹ̀ o si bà le olukuluku wọn. 4 Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si bẹ̀rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn. 5 Awọn Ju olufọkànsin lati orilẹ-ede gbogbo labẹ ọrun si ngbe Jerusalemu. 6 Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀. 7 Hà si ṣe gbogbo wọn, ẹnu si yà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Wo o, ara Galili ki gbogbo awọn ti nsọ̀rọ wọnyi iṣe? 8 Ẽha si ti ṣe ti awa fi ngbọ́ olukuluku li ede wa ninu eyiti a bí wa? 9 Awọn ará Partia, ati Media, ati Elamu, ati awọn ti ngbé Mesopotamia, Judea, ati Kappadokia, Pontu, ati Asia, 10 Frigia, ati Pamfilia, Egipti, ati ẹkùn Libia niha Kirene, ati awọn atipo Romu, awọn Ju ati awọn alawọṣe Ju, 11 Awọn ara Krete ati Arabia, awa gbọ́ nwọn nsọ̀rọ iṣẹ iyanu nla Ọlọrun li ède wa. 12 Hà si ṣe gbogbo wọn, o si rú wọn lojú, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili a le mọ̀ eyi si? 13 Ṣugbọn awọn ẹlomiran nṣẹ̀fẹ nwọn si wipe, Awọn ọkunrin wọnyi kún fun waini titun.

Iwaasu Peteru ní Ọjọ́ Pẹntikọsti

14 Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi: 15 Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi. 16 Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe; 17 Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: 18 Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ: 19 Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn loke li ọrun, ati àmi nisalẹ lori ilẹ: ẹ̀jẹ, ati iná, ati ríru ẹ̃fin; 20 A o sọ õrùn di òkunkun, ati oṣupa di ẹ̀jẹ, ki ọjọ nla afiyesi Oluwa ki o to de: 21 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba pè orukọ Oluwa, a o gbà a là. 22 Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ wọnyi: Jesu ti Nasareti, ọkunrin ti a fi hàn fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá, nipa iṣẹ agbara ati ti iyanu, ati ti àmi ti Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe lãrin nyin, bi ẹnyin tikaranyin ti mọ̀ pẹlu: 23 Ẹniti a ti fi le nyin lọwọ nipa ipinnu ìmọ ati imọtẹlẹ Ọlọrun; on li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa. 24 Ẹniti Ọlọrun gbé dide, nigbati o ti tú irora ikú: nitoriti kò ṣe iṣe fun u lati dì i mu. 25 Nitori Dafidi ti wi nipa tirẹ̀ pe, Mo ri Oluwa nigba-gbogbo niwaju mi, nitoriti o mbẹ li ọwọ́ ọtún mi, ki a mà bà ṣí mi ni ipò: 26 Nitorina inu mi dùn, ahọn mi si yọ̀; pẹlupẹlu ara mi yio si simi ni ireti: 27 Nitoriti iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú, bẹ̃ni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni-Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ. 28 Iwọ mu mi mọ̀ ọ̀na iye; iwọ ó mu mi kún fun ayọ̀ ni iwaju rẹ. 29 Ará, ẹ jẹ ki emi ki o sọ fun nyin gbangba niti Dafidi baba nla pe, o kú, a si sin i, ibojì rẹ̀ si mbẹ lọdọ wa titi o fi di oni yi. 30 Nitoriti iṣe woli, ati bi o ti mọ̀ pe, Ọlọrun ti fi ibura ṣe ileri fun u pe, Ninu irú-ọmọ inu rẹ̀, on ó mu ọ̀kan ijoko lori itẹ́ rẹ̀; 31 O ri eyi tẹlẹ̀, o sọ ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipò-okù, bẹ̃li ara rẹ̀ kò ri idibajẹ. 32 Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe. 33 Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́. 34 Dafidi kò sá gòke lọ si ọrun: ṣugbọn on tikararẹ̀ wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, 35 Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apotì itisẹ rẹ. 36 Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi. 37 Nigbati nwọn si gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn aposteli iyokù pe, Ará, kini ki awa ki o ṣe? 38 Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́. 39 Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè. 40 Ati ọ̀rọ pupọ miran li o fi njẹri ti o si nfi ngbà wọn niyanju wipe, Ẹ gbà ara nyin là lọwọ iran arekereke yi. 41 Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn. 42 Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura. 43 Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe. 44 Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan; 45 Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini. 46 Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn. 47 Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.

Iṣe 3

A Wo Arọ Kan Sàn Lẹ́nu Ọ̀nà Tẹmpili

1 NJẸ Peteru on Johanu jumọ ngòke lọ si tẹmpili ni wakati adura, ti iṣe wakati kẹsan ọjọ. 2 Nwọn si gbé ọkunrin kan ti o yarọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti nwọn ima gbé kalẹ li ojojumọ́ li ẹnu-ọna tẹmpili ti a npè ni Daradara, lati mã ṣagbe lọwọ awọn ti nwọ̀ inu tẹmpili lọ; 3 Nigbati o ri Peteru on Johanu bi nwọn ti fẹ wọ̀ inu tẹmpili, o ṣagbe. 4 Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa. 5 O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn. 6 Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin. 7 O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun. 8 O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun. 9 Gbogbo enia si ri i, o nrìn, o si nyìn Ọlọrun: 10 Nwọn si mọ̀ pe on li o ti joko nṣagbe li ẹnu-ọ̀nà Daradara ti tẹmpili: hà si ṣe wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi si ohun ti o ṣe lara rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ tí Peteru Sọ ní Ìloro Solomoni

11 Bi arọ ti a mu larada si ti di Peteru on Johanu mu, gbogbo enia jumọ sure jọ tọ̀ wọn lọ ni iloro ti a npè ni ti Solomoni, ẹnu yà wọn gidigidi. 12 Nigbati Peteru si ri i, o dahùn wi fun awọn enia pe, Ẹnyin enia Israeli, ẽṣe ti ha fi nṣe nyin si eyi? tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ́ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ́ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrin? 13 Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ. 14 Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin; 15 Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe. 16 Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin. 17 Njẹ nisisiyi, ará, mo mọ̀ pe, nipa aimọ̀ li ẹnyin fi ṣe e, gẹgẹ bi awọn olori nyin pẹlu ti ṣe. 18 Ṣugbọn ohun ti Ọlọrun ti sọ tẹlẹ lati ẹnu gbogbo awọn woli wá pe, Kristi rẹ̀ yio jìya, on li o muṣẹ bẹ̃. 19 Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wá, 20 Ati ki o ba le rán Kristi, ti a ti yàn fun nyin, aní Jesu; 21 Ẹniti ọrun kò le ṣaima gbà titi di igba imupadà ohun gbogbo, ti Ọlọrun ti sọ lati ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́ ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀. 22 Mose sa wipe, Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé woli kan dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ẹnyin o ma gbọ́ tirẹ̀ li ohun gbogbo ti yio ma sọ fun nyin. 23 Yio si ṣe, olukuluku ọkàn ti kò ba gbọ ti woli na, on li a o parun patapata kuro ninu awọn enia. 24 Ani gbogbo awọn woli lati Samueli wá, ati awọn ti o tẹle e, iye awọn ti o ti sọrọ, nwọn sọ ti ọjọ wọnyi pẹlu. 25 Ẹnyin li ọmọ awọn woli, ati ti majẹmu tí Ọlọrun ti ba awọn baba nyin dá nigbati o wi fun Abrahamu pe, Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a ti fi ibukun fun gbogbo idile aiye. 26 Nigbati Ọlọrun jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dide, o kọ́ rán a si nyin lati busi i fun nyin, nipa yiyi olukuluku nyin pada kuro ninu iwa buburu rẹ̀.

Iṣe 4

A Mú Peteru ati Johanu Wá siwaju Ìgbìmọ̀ Àwọn Juu

1 BI nwọn si ti mba awọn enia sọrọ, awọn alufa ati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn Sadusi dide si wọn. 2 Inu bi wọn, nitoriti nwọn nkọ́ awọn enia, nwọn si nwasu ajinde kuro ninu okú ninu Jesu. 3 Nwọn si nawọ́ mu wọn, nwọn si há wọn mọ́ ile tubu titi o fi di ijọ keji: nitoriti alẹ lẹ tan. 4 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn. 5 O si ṣe nijọ keji, awọn olori wọn ati awọn alagba ati awọn akọwe, pejọ si Jerusalemu, 6 Ati Anna olori alufa, ati Kaiafa, ati Johanu, ati Aleksanderu, ati iye awọn ti iṣe ibatan olori alufa. 7 Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi? 8 Nigbana ni Peteru kún fun Ẹmí Mimọ́, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin olori awọn enia, ati ẹnyin àgbagbà. 9 Bi o ba ṣe pe a nwadi wa loni niti iṣẹ rere ti a ṣe lara abirùn na, bi a ti ṣe mu ọkunrin yi laradá; 10 Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa. 11 Eyi li okuta ti a ti ọwọ́ ẹnyin ọmọle kọ̀ silẹ, ti o si di pàtaki igun ile. 12 Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là. 13 Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé. 14 Nigbati nwọn si nwò ọkunrin na ti a mu larada, ti o ba wọn duro, nwọn kò ri nkan wi si i. 15 Ṣugbọn nigbati nwọn si paṣẹ pe ki nwọn jade kuro ni igbimọ, nwọn ba ara wọn gbèro, 16 Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ. 17 Ṣugbọn ki o má bà tàn kalẹ siwaju mọ́ lãrin awọn enia, ẹ jẹ ki a kìlọ fun wọn pe, lati isisiyi lọ ki nwọn ki o máṣe fi orukọ yi sọ̀rọ fun ẹnikẹni mọ́. 18 Nigbati nwọn si pè wọn, nwọn paṣẹ fun wọn, ki nwọn máṣe sọ̀rọ rara, bẹni ki nwọn máṣe kọ́ni li orukọ Jesu mọ́. 19 Ṣugbọn Peteru on Johanu dahùn, nwọn si wi fun wọn pe, Bi o ba tọ́ li oju Ọlọrun lati gbọ́ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò, 20 Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ́. 21 Nigbati nwọn si kìlọ fun wọn si i, nwọn jọwọ wọn lọwọ lọ, nigbati nwọn kò ti ri nkan ti nwọn iba fi jẹ wọn ni ìya, nitori awọn enia: nitori gbogbo wọn ni nyìn Ọlọrun logo fun ohun ti a ṣe. 22 Nitori ọkunrin na jù ẹni-ogoji ọdún lọ, lara ẹniti a ṣe iṣẹ àmi dida ara yi.

Àwọn Onigbagbọ Gbadura fún Ìgboyà

23 Nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn lọ sọdọ awọn ẹgbẹ wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti awọn olori alufa ati awọn agbàgba sọ fun wọn. 24 Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn fi ọkàn kan gbé ohùn wọn soke si Ọlọrun nwọn si wipe, Oluwa, ìwọ ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn: 25 Iwọ nipa Ẹmi Mimọ́ ti o ti ẹnu Dafidi baba wa iranṣẹ rẹ wipe, Ẽṣe ti awọn keferi fi mbinu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan? 26 Awọn ọba aiye dide, ati awọn ijoye kó ara wọn jọ si Oluwa, ati si Kristi rẹ̀; 27 Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si, 28 Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ. 29 Njẹ nisisiyi, Oluwa, kiyesi ikilọ wọn: ki o si fifun awọn ọmọ-ọdọ rẹ lati mã fi igboiya gbogbo sọ ọ̀rọ rẹ. 30 Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ. 31 Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun. 32 Ijọ awọn ti o gbagbọ́ si wà li ọkàn kan ati inu kan: kò si si ẹnikan ti o pè ohun kan ninu ohun ini rẹ̀ ni ti ara rẹ̀: ṣugbọn gbogbo nwọn ni gbogbo nkan ṣọkan. 33 Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn. 34 Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá. 35 Nwọn si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli: nwọn si npín fun olukuluku, gẹgẹ bi o ti ṣe alaini si. 36 Ati Josefu, ti a ti ọwọ awọn aposteli sọ apele rẹ̀ ni Barnaba (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ọmọ-Itùnu), ẹ̀ya Lefi, ati ara Kipru. 37 O ni ilẹ kan, o tà a, o mu owo rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli.

Iṣe 5

Anania ati Safira

1 ṢUGBỌN ọkunrin kan ti a npè ni Anania, pẹlu Safira aya rẹ̀, tà ilẹ iní kan. 2 O si yàn apakan pamọ́ ninu owo na, aya rẹ̀ ba a mọ̀ ọ pọ̀, o si mu apakan rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli. 3 Ṣugbọn Peteru wipe, Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmí Mimọ́, ti iwọ si fi yàn apakan pamọ́ ninu owo ilẹ na? 4 Nigbati o wà nibẹ, tirẹ ki iṣe? nigbati a si ta a tan, kò ha wà ni ikawọ ara rẹ? Ẽha ti ṣe ti iwọ fi rò kini yi li ọkàn rẹ? enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun. 5 Nigbati Anania si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o ṣubu lulẹ, o si kú: ẹ̀ru nla si ba gbogbo awọn ti o gbọ́. 6 Awọn ọdọmọkunrin si dide, nwọn dì i, nwọn si gbé e jade, nwọn si sin i. 7 O si to bi ìwọn wakati mẹta, aya rẹ̀ laimọ̀ ohun ti o ti ṣe, o wọle. 8 Peteru si da a lohùn pe, Wi fun mi, bi iye bayi li ẹnyin tà ilẹ na? O si wipe, Lõtọ iye bẹ̃ ni. 9 Peteru si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fohùn ṣọkan lati dán Ẹmí Oluwa wò? wò o, ẹsẹ awọn ti o sinkú ọkọ rẹ mbẹ li ẹnu ọ̀na, nwọn o si gbé ọ jade. 10 O si ṣubu lulẹ li ẹsẹ rẹ̀ lojukanna, o si kú: awọn ọdọmọkunrin si wọle, nwọn bá a o kú, nwọn si gbé e jade, nwọn sin i lẹba ọkọ rẹ̀. 11 Ẹru nla si ba gbogbo ijọ, ati gbogbo awọn ti o gbọ́ nkan wọnyi.

Àwọn Aposteli Ṣe Iṣẹ́ Àmì Pupọ

12 A si ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu pipọ lãrin awọn enia: gbogbo wọn si fi ọkàn kan wà ni iloro Solomoni. 13 Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn: ṣugbọn enia nkókiki wọn. 14 A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin; 15 Tobẹ̃ ti nwọn ngbé awọn abirùn jade si igboro, ti nwọn ntẹ́ wọn si ori akete ati ohun ibĩrọgbọku, pe bi Peteru ba nkọja ki ojiji rẹ̀ tilẹ le ṣijibò omiran ninu wọn. 16 Ọ̀pọ enia si ko ara wọn jọ lati awọn ilu ti o yi Jerusalemu ka, nwọn nmu awọn abirùn wá, ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si ṣe dida ara olukuluku wọn.

A Ṣe Inúnibíni sí Àwọn Aposteli

17 Ṣugbọn olori alufa dide, ti on ti gbogbo awọn ti nwọn wà lọdọ rẹ̀ (ti iṣe ẹya ti awọn Sadusi), nwọn si kún fun owu. 18 Nwọn si nawọ́ mu awọn aposteli, nwọn si fi wọn sinu tubu. 19 Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe, 20 Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mã sọ gbogbo ọ̀rọ iye yi fun awọn enia ni tẹmpili. 21 Nigbati nwọn si gbọ́ yi, nwọn wọ̀ tẹmpili lọ ni kutukutu, nwọn si nkọ́ni. Ṣugbọn olori alufa de, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si pè apejọ igbimọ, ati gbogbo awọn agbàgba awọn ọmọ Israeli, nwọn si ranṣẹ si ile tubu lati mu wọn wá. 22 Ṣugbọn nigbati awọn onṣẹ de ibẹ̀, nwọn kò si ri wọn ninu tubu, nwọn pada wá, nwọn si sọ pe, 23 Awa bá ile tubu o sé pinpin, ati awọn oluṣọ duro lode niwaju ilẹkun: ṣugbọn nigbati awa ṣílẹkun, awa kò bá ẹnikan ninu tubu. 24 Nigbati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn olori alufa si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn dãmu nitori wọn pe, nibo li eyi ó yọri si. 25 Nigbana li ẹnikan de, o wi fun wọn pe, Wo o, awọn ọkunrin ti ẹnyin fi sinu tubu wà ni tẹmpili, nwọn duro nwọn si nkọ́ awọn enia. 26 Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta. 27 Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn lẽre, 28 Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa. 29 Ṣugbọn Peteru ati awọn aposteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ. 30 Ọlọrun awọn baba wa ji Jesu dide, ẹniti ẹnyin pa, tí ẹnyin si gbe kọ́ sori igi. 31 On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ. 32 Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀. 33 Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn. 34 Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ; 35 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ọkunrin Israeli, ẹ kiyesi ara nyin li ohun ti ẹnyin npete ati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi. 36 Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan. 37 Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká. 38 Njẹ emi wi fun nyin nisisiyi, Ẹ gafara fun awọn ọkunrin wọnyi, ki ẹ si jọwọ wọn jẹ: nitori bi ìmọ tabi iṣẹ yi ba jẹ ti enia, a o bì i ṣubu: 39 Ṣugbọn bi ti Ọlọrun ba ni, ẹnyin kì yio le bì i ṣubu; ki o ma ba jẹ pe, a ri nyin ẹ mba Ọlọrun jà. 40 Nwọn si tẹ̀ si tirẹ̀: nigbati nwọn si pè awọn aposteli wọle, nwọn lù wọn, nwọn si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ li orukọ Jesu mọ́, nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. 41 Nitorina nwọn si lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: nwọn nyọ̀ nitori ti a kà wọn yẹ si ìya ijẹ nitori orukọ rẹ̀. 42 Ati li ojojumọ́ ni tẹmpili ati ni ile, nwọn kò dẹkun ikọ́ni, ati lati wasu Jesu Kristi.

Iṣe 6

A Yan Àwọn Olùrànlọ́wọ́ Meje

1 NJẸ li ọjọ wọnni, nigbati iye awọn ọmọ-ẹhin npọ̀ si i, ikùn-sinu wà ninu awọn Hellene si awọn Heberu, nitoriti a nṣe igbagbé awọn opó wọn ni ipinfunni ojojumọ́. 2 Awọn mejila si pè ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin jọ̀ sọdọ, nwọn wipe, Kò yẹ ti awa iba fi ọ̀rọ Ọlọrun silẹ, ki a si mã ṣe iranṣẹ tabili. 3 Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ ati fun ọgbọ́n, ẹniti awa iba yàn si iṣẹ yi. 4 Ṣugbọn awa o duro ṣinṣin ninu adura igbà, ati ninu iṣẹ iranṣẹ ọ̀rọ na. 5 Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku: 6 Ẹniti nwọn mu duro niwaju awọn aposteli: nigbati nwọn si gbadura, nwọn fi ọwọ́ le wọn. 7 Ọ̀rọ Ọlọrun si gbilẹ; iye awọn ọmọ-ẹhin si pọ̀ si i gidigidi ni Jerusalemu; ọ̀pọ ninu ẹgbẹ awọn alufa si fetisi ti igbagbọ́ na.

Àwọn Aṣiwaju Àwọn Juu Mú Stefanu

8 Ati Stefanu, ti o kún fun ore-ọfẹ ati agbara, o ṣe iṣẹ iyanu, ati iṣẹ ami nla lãrin awọn enia. 9 Ṣugbọn awọn kan dide ninu awọn ti sinagogu, ti a npè ni ti awọn Libertine, ati ti ara Kirene, ati ti ara Aleksandria, ati ninu awọn ara Kilikia, ati ti Asia nwọn mba Stefanu jiyàn. 10 Nwọn kò si le kò ọgbọ́n ati ẹmí ti o fi nsọrọ loju. 11 Nigbana ni nwọn bẹ̀ abẹtẹlẹ awọn ọkunrin, ti nwọn nwipe, Awa gbọ́ ọkunrin yi nsọ ọrọ-odi si Mose ati si Ọlọrun. 12 Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ. 13 Nwọn si mu awọn ẹlẹri eke wá, ti nwọn wipe, ọkunrin yi kò simi lati sọ ọ̀rọ-òdi si ibi mimọ́ yi, ati si ofin: 14 Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà. 15 Ati gbogbo awọn ti o si joko ni ajọ igbimọ tẹjumọ́ ọ, nwọn nwò oju rẹ̀ bi ẹnipe oju angẹli.

Iṣe 7

Ọ̀rọ̀ Tí Stefanu Sọ

1 NIGBANA li olori alufa wipe, Nkan wọnyi ha ri bẹ̃ bi? 2 On si wipe, Alàgba, ará, ati baba, ẹ fetisilẹ̀; Ọlọrun ogo fi ara hàn fun Abrahamu baba wa, nigbati o wà ni Mesopotamia, ki o to ṣe atipo ni Harani, 3 O si wi fun u pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati lọdọ awọn ibatan rẹ, ki o si wá si ilẹ ti emi ó fi hàn ọ. 4 Nigbana li o jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, o si ṣe atipo ni Harani: lẹhin igbati baba rẹ̀ kú, Ọlọrun mu u ṣipo pada wá si ilẹ yi, nibiti ẹnyin ngbé nisisiyi. 5 Kò si fun u ni ini kan, ani to bi ẹsẹ ilẹ kan; ṣugbọn o leri pe, on ó fi i fun u ni ilẹ-nini, ati fun awọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati kò ti ili ọmọ. 6 Ọlọrun si sọ bayi pe, irú-ọmọ rẹ̀ yio ṣe atipo ni ilẹ àjeji; nwọn ó si sọ wọn di ẹru, nwọn o si pọ́n wọn loju ni irinwo ọdún. 7 Ọlọrun wipe, Orilẹ-ède na ti nwọn o ṣe ẹrú fun, li emi ó da lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade kuro, nwọn o si wá sìn mi nihinyi. 8 O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila. 9 Awọn baba nla si ṣe ilara Josefu, nwọn si tà a si Egipti: ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. 10 O si yọ ọ kuro ninu ipọnju rẹ̀ gbogbo, o si fun u li ojurere ati ọgbọ́n li oju Farao ọba Egipti; on si fi i jẹ bãlẹ Egipti ati gbogbo ile rẹ̀. 11 Iyan kan si wá imu ni gbogbo ilẹ Egipti ati ni Kenaani, ati ipọnju pipọ: awọn baba wa kò si ri onjẹ. 12 Ṣugbọn nigbati Jakọbu gbọ́ pe alikama mbẹ ni Egipti, o rán awọn baba wa lọ lẹrinkini. 13 Ati nigba keji Josefu fi ara rẹ̀ hàn fun awọn arakunrin rẹ̀; a si fi awọn ará Josefu hàn fun Farao. 14 Josefu si ranṣẹ, o si pè Jakọbu baba rẹ̀, ati gbogbo awọn ibatan rẹ̀ sọdọ rẹ̀, arundilọgọrin ọkàn. 15 Jakọbu si sọkalẹ lọ si Egipti, o si kú, on ati awọn baba wa, 16 A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu. 17 Ṣugbọn bi akokò ileri ti Oluwa ṣe fun Abrahamu ti kù si dẹ̀dẹ, awọn enia na nrú, nwọn si nrẹ̀ ni Egipti, 18 Titi ọba miran fi jẹ lori Egipti ti kò mọ̀ Josefu. 19 On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè. 20 Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀: 21 Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀. 22 A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe. 23 Nigbati o si di ẹni iwọn ogoji ọdún, o sọ si i lọkan lati lọ ibẹ̀ awọn ọmọ Israeli ará rẹ̀ wò. 24 Nigbati o si ri ọkan ninu wọn ti a njẹ ni ìya, o gbejà rẹ̀, o gbẹsan ẹniti nwọn njẹ ni ìya, o si lu ara Egipti na pa: 25 O si ṣebi awọn ará on mọ̀ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ́ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn kò mọ̀. 26 O si di ijọ keji o yọ si wọn bi nwọn ti njà, on iba si pari rẹ̀ fun wọn, o wipe, Alàgba, ará li ẹnyin; ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ohun ti kò tọ́ si ara nyin? 27 Ṣugbọn ẹniti o finran si ẹnikeji rẹ̀ tì i kuro, o wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ wa? 28 Iwọ nfẹ pa mi gẹgẹ bi o ti pa ará Egipti laná? 29 Mose si sá nitori ọ̀rọ yi, o si wa ṣe atipo ni ilẹ Midiani, nibiti o gbé bí ọmọ meji. 30 Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́. 31 Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i, 32 Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́. 33 Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni. 34 Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti. 35 Mose na yi ti nwọn kọ̀, wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ? on na li Ọlọrun rán lọ lati ọwọ́ angẹli, ti o farahàn a ni igbẹ́, lati ṣe olori ati oludande. 36 On li o mu wọn jade, lẹhin igbati o ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi ni ilẹ Egipti, ati li Okun pupa, ati li aginjù li ogoji ọdún. 37 Eyi ni Mose na ti o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Woli kan li Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ki ẹ gbọ́ tirẹ. 38 Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọ̀rọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọ̀rọ ìye lati fifun wa: 39 Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti; 40 Nwọn wi fun Aaroni pe, Dà oriṣa fun wa ti yio ma tọ̀na ṣaju wa: nitori bi o ṣe ti Mose yi ti o mu wa ti ilẹ Egipti jade wá, a kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. 41 Nwọn si yá ere ẹgbọ̀rọ malu ni ijọ wọnni, nwọn si rubọ si ere na, nwọn si nyọ̀ ninu iṣẹ ọwọ́ ara wọn. 42 Ọlọrun si pada, o fi wọn silẹ lati mã sìn ogun ọrun; bi a ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, Ẹnyin ara ile Israeli, ẹnyin ha mu ẹran ti a pa ati ẹbọ fun mi wá bi li ogoji ọdun ni iju? 43 Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni. 44 Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri; 45 Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi; 46 Ẹniti o ri ojurere niwaju Ọlọrun, ti o si tọrọ lati ri ibugbe fun Ọlọrun Jakọbu. 47 Ṣugbọn Solomoni kọ́ ile fun u. 48 Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe, 49 Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi? 50 Ọwọ́ mi kọ́ ha ṣe gbogbo nkan wọnyi? 51 Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin. 52 Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa: 53 Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́.

Wọ́n Sọ Stefanu ní Òkúta Pa

54 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke. 55 Ṣugbọn on kún fun Ẹmí Mimọ́, o tẹjumọ́ ọrun, o si ri ogo Ọlọrun, ati Jesu nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun. 56 O si wipe, Wò o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun. 57 Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara, nwọn si dì eti wọn, nwọn si fi ọkàn kan rọ́ lù u, 58 Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu. 59 Nwọn sọ Stefanu li okuta, o si nképe Oluwa wipe, Jesu Oluwa, gbà ẹmí mi. 60 O si kunlẹ, o kigbe li ohùn rara pe, Oluwa, má kà ẹ̀ṣẹ yi si wọn li ọrùn. Nigbati o si wi eyi, o sùn.

Iṣe 8

Saulu Ṣe Inúnibíni Sí Ìjọ Kristi

1 SAULU si li ohùn si ikú rẹ̀. Li akoko na, inunibini nla kan dide si ijọ ti o wà ni Jerusalemu; a si tú gbogbo wọn kalẹ já àgbegbe Judea on Samaria, afi awọn aposteli. 2 Awọn enia olufọkànsin si dì okú Stefanu, nwọn si pohùnrére ẹkún kikan sori rẹ̀. 3 Ṣugbọn Saulu, o ndà ijọ enia Ọlọrun ru, o nwọ̀ ojõjũle, o si nmu awọn ọkunrin ati obinrin, o si nfi wọn sinu tubu.

A Waasu Ìhìn Rere ní Samaria

4 Awọn ti nwọn si túka lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọ̀rọ na. 5 Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn. 6 Awọn ijọ enia si fi ọkàn kan fiyesi ohun ti Filippi nsọ, nigbati nwọn ngbọ́, ti nwọn si ri iṣẹ ami ti o nṣe. 7 Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn. 8 Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na. 9 Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on: 10 Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla. 11 On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn. 12 Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin. 13 Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a. 14 Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn: 15 Awọn ẹniti o si gbadura fun wọn, nigbati nwọn sọkalẹ, ki nwọn ki o le ri Ẹmí Mimọ́ gbà: 16 Nitori titi o fi di igbana kò ti ibà le ẹnikẹni ninu wọn; kìki a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa ni. 17 Nigbana ni nwọn gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si gbà Ẹmí Mimọ́. 18 Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn. 19 O wipe, Ẹ fun emi na ni agbara yi pẹlu, ki ẹnikẹni ti mo ba gbe ọwọ́ le, ki o le gbà Ẹmí Mimọ́. 20 Ṣugbọn Peteru da a lohùn wipe, Ki owo rẹ ṣegbé pẹlu rẹ, nitoriti iwọ rò lati fi owo rà ẹ̀bun Ọlọrun. 21 Iwọ kò ni ipa tabi ipín ninu ọ̀ràn yi: nitori ọkàn rẹ kò ṣe dédé niwaju Ọlọrun. 22 Nitorina ronupiwada ìwa buburu rẹ yi, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yio dari ete ọkàn rẹ jì ọ. 23 Nitoriti mo woye pe, iwọ wà ninu ikorò orõro, ati ni ìde ẹ̀ṣẹ. 24 Nigbana ni Simoni dahùn, o si wipe, Ẹ gbadura sọdọ Oluwa fun mi, ki ọ̀kan ninu ohun ti ẹnyin ti sọ ki o máṣe ba mi. 25 Ati awọn nigbati nwọn si ti jẹri, ti nwọn si ti sọ ọrọ Oluwa, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si wasu ihinrere ni iletò pipọ ti awọn ara Samaria.

Filipi ati Ìwẹ̀fà Ará Etiopia

26 Angẹli Oluwa si sọ fun Filippi, pe, Dide ki o si ma lọ si ìha gusu li ọ̀na ti o ti Jerusalemu lọ si Gasa, ti iṣe ijù. 27 Nigbati o si dide, o lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan ara Etiopia, iwẹfa ọlọlá pipọ lọdọ Kandake ọbabirin awọn ara Etiopia, ẹniti iṣe olori gbogbo iṣura rẹ̀, ti o si ti wá si Jerusalemu lati jọsin, 28 On si npada lọ, o si joko ninu kẹkẹ́ rẹ̀, o nkà iwe woli Isaiah. 29 Ẹmí si wi fun Filippi pe, Lọ ki o si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹkẹ́ yi. 30 Filippi si sure lọ, o gbọ́, o nkà iwe woli Isaiah, o si bi i pe, Ohun ti iwọ nkà nì, o yé ọ? 31 O si dahùn wipe, Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ́ mi si ọna? O si bẹ̀ Filippi ki o gòke wá, ki o si ba on joko. 32 Ibi iwe-mimọ́ ti o si nkà na li eyi, A fà a bi agutan lọ fun pipa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀: 33 Ni irẹsilẹ rẹ̀ a mu idajọ kuro: tani yio sọ̀rọ iran rẹ̀? nitori a gbà ẹmí rẹ̀ kuro li aiye. 34 Iwẹfa si da Filippi lohùn, o ni, Mo bẹ̀ ọ, ti tani woli na sọ ọ̀rọ yi? ti ara rẹ̀, tabi ti ẹlomiran? 35 Filippi si yà ẹnu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ lati ibi iwe-mimọ́ yi, o si wasu Jesu fun u. 36 Bi nwọn si ti nlọ li ọ̀na, nwọn de ibi omi kan: iwẹfa na si wipe, Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi? 37 Filippi si wipe, Bi iwọ ba gbagbọ́ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ. O si dahùn o ni, Mo gbagbọ́ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni. 38 O si paṣẹ ki kẹkẹ́ duro jẹ: awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa; o si baptisi rẹ̀. 39 Nigbati nwọn si jade kuro ninu omi, Ẹmí Oluwa ta Filippi pá, iwẹfa kò si ri i mọ́: nitoriti o mbá ọ̀na rẹ̀ lọ, o nyọ̀. 40 Ni Asotu li a si ri Filippi; bi o si ti nkọja lọ, o nwasu ihinrere ni gbogbo ilu, titi o fi de Kesarea.

Iṣe 9

Saulu di Onigbagbọ

1 ṢUGBỌN Saulu, o nmí ẹmi ikilọ ati pipa sibẹ si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa, o tọ̀ olori alufa lọ; 2 O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu. 3 O si ṣe, bi o ti nlọ, o si sunmọ Damasku: lojijì lati ọrun wá, imọlẹ si mọlẹ yi i ka: 4 O si ṣubu lulẹ, o gbọ́ ohùn ti o nfọ̀ si i pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? 5 O si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. 6 O si nwarìri, ẹnu si yà a, o ni, Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe? Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ilu na, a o sọ fun ọ li ohun ti iwọ o ṣe. 7 Awọn ọkunrin ti nwọn si mba a re àjo duro, kẹ́kẹ pa mọ́ wọn li ẹnu, nwọn gbọ́ ohùn na, ṣugbọn nwọn kò ri ẹnikan. 8 Saulu si dide ni ilẹ; nigbati oju rẹ̀ si là kò ri ohunkan: ṣugbọn nwọn fà a li ọwọ́, nwọn si mu u wá si Damasku. 9 O si gbé ijọ mẹta li airiran, kò si jẹ, bẹ̃ni kò si mu. 10 Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò o, emi niyi, Oluwa. 11 Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura. 12 On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́ le e, ki o le riran. 13 Anania si dahùn wipe, Oluwa, mo ti gburó ọkunrin yi lọdọ ọ̀pọ enia, gbogbo buburu ti o ṣe si awọn enia mimọ́ rẹ ni Jerusalemu. 14 O si gbà aṣẹ lati ọdọ awọn olori alufa wá si ihinyi, lati dè gbogbo awọn ti npè orukọ rẹ. 15 Ṣugbọn Oluwa wi fun u pe, Mã lọ: nitori ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israeli: 16 Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a. 17 Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́. 18 Lojukanna nkan si bọ kuro li oju rẹ̀ bi ipẹpẹ́: o si riran; o si dide, a si baptisi rẹ̀. 19 Nigbati o si jẹun, ara rẹ̀ mokun: Saulu si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Damasku ni ijọ melokan. 20 Lojukanna o si nwasu Kristi ninu awọn sinagogu pe, Ọmọ Ọlọrun li on iṣe. 21 Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa? 22 Ṣugbọn Saulu npọ̀ si i li agbara o si ndãmu awọn Ju ti o ngbe Damasku, o nfi hàn pe, eyi ni Kristi na.

Saulu Bọ́ lọ́wọ́ Àwọn Juu

23 Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a: 24 Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a. 25 Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n.

Saulu Pada Dé Jerusalẹmu

26 Nigbati Saulu si de Jerusalemu, o pete ati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ-ẹhin: gbogbo nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, nitori nwọn kò gbagbọ́ pe ọmọ-ẹhin kan ni. 27 Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu. 28 O si wà pẹlu wọn, o nwọle o si njade ni Jerusalemu. 29 O si nfi igboiya sọ̀rọ li orukọ Jesu Oluwa, o nsọrọ lòdi si awọn ara Hellene, o si njà wọn niyàn: ṣugbọn nwọn npete ati pa a. 30 Nigbati awọn arakunrin si mọ̀, nwọn mu u sọkalẹ lọ si Kesarea, nwọn si rán a lọ si Tarsu. 31 Nigbana ni ijọ wà li alafia yi gbogbo Judea ká ati ni Galili ati ni Samaria, nwọn nfẹsẹmulẹ; nwọn nrìn ni ìbẹru Oluwa, ati ni itunu Ẹmí Mimọ́, nwọn npọ̀ si i.

Peteru Mú Enea Láradá

32 O si ṣe, bi Peteru ti nkọja nlà ẹkùn gbogbo lọ, o sọkalẹ tọ̀ awọn enia mimọ́ ti ngbe Lidda pẹlu. 33 Nibẹ̀ li o ri ọkunrin kan ti a npè ni Enea ti o ti dubulẹ lori akete li ọdún mẹjọ, o ni àrun ẹ̀gba. 34 Peteru si wi fun u pe, Enea, Jesu Kristi mu ọ larada: dide, ki o si tún akete rẹ ṣe. O si dide lojukanna. 35 Gbogbo awọn ti ngbe Lidda ati Saroni si ri i, nwọn si yipada si Oluwa.

Peteru Jí Dorka Dìde

36 Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Joppa ti a npè ni Tabita, ni itumọ̀ rẹ̀ ti a npè ni Dorka: obinrin yi pọ̀ ni iṣẹ ore, ati itọrẹ-ãnu ti o ṣe. 37 O si ṣe ni ijọ wọnni, ti o ṣaisàn, o si kú: nigbati nwọn wẹ̀ ẹ tan, nwọn tẹ́ ẹ si yara kan loke. 38 Bi Lidda si ti sunmọ Joppa, nigbati awọn ọmọ-ẹhin gbọ́ pe Peteru wà nibẹ̀, awọn rán ọkunrin meji si i lọ ibẹ̀ ẹ pe, Máṣe jafara ati de ọdọ wa. 39 Peteru si dide, o si bá wọn lọ. Nigbati o de, nwọn mu u lọ si yara oke na: gbogbo awọn opó si duro tì i, nwọn nsọkun, nwọn si nfi ẹ̀wu ati aṣọ ti Dorka dá hàn a, nigbati o wà pẹlu wọn. 40 Ṣugbọn Peteru ti gbogbo wọn sode, o si kunlẹ, o si gbadura; o si yipada si okú, o ni, Tabita, dide. O si là oju rẹ̀: nigbati o si ri Peteru, o dide joko. 41 O si nà ọwọ́ rẹ̀ si i, o fà a dide; nigbati o si pè awọn enia mimọ́ ati awọn opó, o fi i le wọn lọwọ lãye. 42 O si di mimọ̀ yi gbogbo Joppa ká; ọpọlọpọ si gba Oluwa gbọ́. 43 O si ṣe, o gbé ọjọ pipọ ni Joppa lọdọ ọkunrin kan Simoni alawọ.

Iṣe 10

Ìtàn Peteru ati Korneliu

1 ỌKUNRIN kan si wà ni Kesarea ti a npè ni Korneliu, balogun ọrún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti a npè ni ti Itali, 2 Olufọkansìn, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹniti o nṣe itọrẹ-ãnu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigbagbogbo. 3 Niwọn wakati kẹsan ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Korneliu. 4 Nigbati o si tẹjumọ́ ọ, ti ẹ̀ru si ba a, o ni, Kini, Oluwa? O si wi fun u pe, Adura rẹ ati ọrẹ-ãnu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlọrun fun iranti. 5 Si rán enia nisisiyi lọ si Joppa, ki nwọn si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru: 6 O wọ̀ si ile ẹnikan Simoni alawọ, ti ile rẹ̀ wà leti okun: on ni yio sọ fun ọ bi iwọ o ti ṣe. 7 Nigbati angẹli na ti o ba Korneliu sọ̀rọ si fi i silẹ lọ, o pè meji ninu awọn iranṣẹ ile rẹ̀, ati ọmọ-ogun olufọkànsin kan, ninu awọn ti ima duro tì i nigbagbogbo; 8 Nigbati o si ti rohin ohun gbogbo fun wọn, o rán wọn lọ si Joppa. 9 Ni ijọ keji bi nwọn ti nlọ li ọ̀na àjo wọn, ti nwọn si sunmọ ilu na, Peteru gùn oke ile lọ igbadura niwọn wakati kẹfa ọjọ: 10 Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran, 11 O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ. 12 Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun. 13 Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ. 14 Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri. 15 Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́. 16 Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: lojukanna a si gbé ohun elo na pada lọ soke ọrun. 17 Bi o si ti ngọ́ Peteru ninu ara rẹ̀ bi a ba ti mọ̀ iran ti on ri yi si, si wo o, awọn ọkunrin ti a rán ti ọdọ Korneliu wá de, nwọn mbère ile Simoni, nwọn duro li ẹnu-ọ̀na, 18 Nwọn nahùn bère bi Simoni ti a npè ni Peteru, wọ̀ nibẹ. 19 Bi Peteru si ti nronu iran na, Ẹmí wi fun u pe, Wo o, awọn ọkunrin mẹta nwá ọ. 20 Njẹ dide, sọkalẹ ki o si ba wọn lọ, máṣe kọminu ohunkohun: nitori emi li o rán wọn. 21 Nigbana ni Peteru sọkalẹ tọ̀ awọn ọkunrin ti a rán si i lati ọdọ Korneliu wá; o ni, Wo o, emi li ẹniti ẹnyin nwá: ere idi rẹ̀ ti ẹ fi wá? 22 Nwọn si wipe, Korneliu balogun ọrún, ọkunrin olõtọ, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si ni orukọ rere lọdọ gbogbo orilẹ-ede awọn Ju, on li a ti ọdọ Ọlọrun kọ́ nipasẹ angẹli mimọ́, lati ranṣẹ pè ọ wá si ile rẹ̀ ati lati gbọ́ ọ̀rọ li, ẹnu rẹ. 23 Nigbana li o pè wọn wọle, o si fi wọn wọ̀. Nijọ keji o si dide, o ba wọn lọ, ninu awọn arakunrin ni Joppa si ba a lọ. 24 Nijọ keji nwọn si wọ̀ Kesarea. Korneliu si ti nreti wọn, o si ti pè awọn ibatan ati awọn ọrẹ́ rẹ̀ timọtimọ jọ. 25 O si ṣe bi Peteru ti nwọle, Korneliu pade rẹ̀, o wolẹ li ẹsẹ rẹ̀, o si foribalẹ fun u. 26 Ṣugbọn Peteru gbé e dide, o ni, Dide; enia li emi tikarami pẹlu. 27 Bi o si ti mba a sọ̀rọ, o wọle, o si bá awọn enia pipọ ti nwọn pejọ. 28 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́. 29 Nitorina ni mo si ṣe wá li aijiyàn, bi a ti ranṣẹ pè mi: njẹ mo bère, nitori kili ẹnyin ṣe ranṣẹ pè mi? 30 Korneliu si dahùn pe, Ni ijẹrin, mo nṣe adura wakati kẹsan ọjọ ni ile mi titi di akoko yi, si wo o, ọkunrin kan alaṣọ àla duro niwaju mi. 31 O si wipe, Korneliu, a gbọ́ adura rẹ, ọrẹ-ãnu rẹ si wà ni iranti niwaju Ọlọrun. 32 Njẹ ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru; o wọ̀ ni ile Simoni alawọ leti okun: nigbati o ba de, yio sọ̀rọ fun ọ. 33 Nitorina ni mo si ti ranṣẹ si ọ lojukanna, iwọ si ṣeun ti o fi wá. Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ́ ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá.

Ọ̀rọ̀ Tí Peteru Sọ nílé Korneliu

34 Peteru si yà ẹnu rẹ̀, o si wipe, Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojuṣaju enia: 35 Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bẹ̀ru rẹ̀, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀. 36 Ọ̀rọ ti Ọlọrun rán si awọn ọmọ Israeli, nigbati o wasu alafia nipa Jesu Kristi (on li Oluwa ohun gbogbo), 37 Ẹnyin na mọ̀ ọ̀rọ na ti a kede rẹ̀ yiká gbogbo Judea, ti a bẹ̀rẹ si lati Galili wá, lẹhin baptismu ti Johanu wasu rẹ̀; 38 Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. 39 Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o ṣe, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu; ẹniti nwọn pa, ti nwọn si fi gbékọ sori igi: 40 On li Ọlọrun jinde ni ijọ kẹta, o si fi i hàn gbangba: 41 Kì iṣe fun gbogbo enia, bikoṣe fun awọn ẹlẹri ti a ti ọwọ Ọlọrun yàn tẹlẹ, fun awa, ti a ba a jẹ, ti a si ba a mu lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú. 42 O si paṣẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ ãye on okú. 43 On ni gbogbo awọn woli jẹri si pe, nipa orukọ rẹ̀ li ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ, yio ri imukuro ẹ̀ṣẹ gbà.

Àwọn Tí Kì í ṣe Juu Gba Ẹ̀mí Mímọ́

44 Bi Peteru si ti nsọ ọ̀rọ wọnyi li ẹnu, Ẹmí Mimọ́ bà le gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na. 45 Ẹnu si yà awọn onigbagbọ ti ìkọlà, iye awọn ti o ba Peteru wá, nitoriti a tu ẹbùn Ẹmi Mimọ́ sori awọn Keferi pẹlu. 46 Nitori nwọn gbọ́, nwọn nfọ onirũru ède, nwọn si nyìn Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahùn wipe, 47 Ẹnikẹni ha le ṣòfin omi, ki a má baptisi awọn wọnyi, ti nwọn gbà Ẹmí Mimọ́ bi awa? 48 O si paṣẹ ki a baptisi wọn li orukọ Jesu Kristi. Nigbana ni nwọn bẹ̀ ẹ ki o duro ni ijọ melokan.

Iṣe 11

Peteru Ròhìn fún Ìjọ ní Jerusalẹmu

1 AWỌN aposteli ati awọn arakunrin ti o wà ni Judea si gbọ́ pe awọn Keferi pẹlu ti gba ọ̀rọ Ọlọrun. 2 Nigbati Peteru si gòke wá si Jerusalemu, awọn ti ikọla mba a sọ, 3 Wipe, Iwọ wọle tọ̀ awọn enia alaikọlà lọ, o si ba wọn jẹun. 4 Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe, 5 Emi wà ni ilu Joppa, mo ngbadura: mo ri iran kan li ojuran, Ohun elo kan sọkalẹ bi gọgọwu nla, ti a ti igun mẹrẹrin sọ̀ ka ilẹ lati ọrun wá; o si wá titi de ọdọ mi: 6 Mo tẹjumọ ọ, mo si fiyesi i, mo si ri ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aiye, ati ẹranko igbẹ́, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju ọrun. 7 Mo si gbọ́ ohùn kan ti o fọ̀ si mi pe, Dide, Peteru; mã pa, ki o si mã jẹ. 8 Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai. 9 Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ. 10 Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: a sì tun fà gbogbo rẹ̀ soke ọrun. 11 Si wo o, lojukanna ọkunrin mẹta duro niwaju ile ti a gbé wà, ti a rán lati Kesarea si mi. 12 Ẹmí si wi fun mi pe, ki emi ki o ba wọn lọ, ki emi máṣe kọminu ohunkohun. Awọn arakunrin mẹfa wọnyi si ba mi lọ, a si wọ̀ ile ọkunrin na: 13 O si sọ fun wa bi on ti ri angẹli kan ti o duro ni ile rẹ̀, ti o si wipe, Ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni ti apele rẹ̀ jẹ Peteru; 14 Ẹniti yio sọ ọ̀rọ fun ọ, nipa eyiti a o fi gbà iwọ ati gbogbo ile rẹ là. 15 Bi mo si ti bẹ̀rẹ si isọ, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn, gẹgẹ bi o ti bà le wa li àtetekọṣe. 16 Nigbana ni mo ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wipe, Johanu fi omi baptisi nitõtọ; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin. 17 Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹ̀bun kanna fun wọn ti o ti fifun awa pẹlu nigbati a gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, tali emi ti emi ó fi le dè Ọlọrun li ọ̀na? 18 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́, nwọn si yìn Ọlọrun logo wipe, Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si ìye fun awọn Keferi pẹlu.

Ìjọ ní Antioku

19 Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju. 20 Ṣugbọn awọn kan mbẹ ninu wọn ti iṣe ara Kipru, ati Kirene; nigbati nwọn de Antioku nwọn sọ̀rọ fun awọn Hellene pẹlu, nwọn nwasu Jesu Oluwa. 21 Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu wọn: ọpọlọpọ awọn ti o gbagbọ́ yipada si Oluwa. 22 Ihìn wọn si de etí ijọ ti o wà ni Jerusalemu: nwọn si rán Barnaba lọ titi de Antioku; 23 Ẹniti, nigbati o de ti o si ri õre-ọfẹ Ọlọrun, o yọ̀, o si gba gbogbo wọn niyanju pe, pẹlu ipinnu ọkàn ni ki nwọn ki o fi ara mọ́ Oluwa. 24 Nitori on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmí Mimọ́, ati fun igbagbọ́: enia pipọ li a si kà kún Oluwa. 25 Barnaba si jade lọ si Tarsu lati wá Saulu. 26 Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian. 27 Li ọjọ wọnni li awọn woli si ti Jerusalemu sọkalẹ wá si Antioku. 28 Nigbati ọkan ninu wọn, ti a npè ni Agabu si dide, o tipa Ẹmi sọ pe, ìyan nla yio mu ká gbogbo aiye: eyiti o si ṣẹ li ọjọ Klaudiu Kesari. 29 Awọn ọmọ-ẹhin si pinnu, olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti to, lati rán iranlọwọ si awọn arakunrin ti o wà ni Judea: 30 Eyiti nwọn si ṣe, nwọn si fi i ranṣẹ si awọn àgba lati ọwọ́ Barnaba on Saulu.

Iṣe 12

Inúnibíni sí ìjọ

1 LI akoko igbana ni Herodu ọba si nawọ́ rẹ̀ lati pọn awọn kan loju ninu ijọ. 2 O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johanu. 3 Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ́ mu Peteru pẹlu. O si jẹ ìgba ọjọ àiwukàra. 4 Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja. 5 Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u.

Peteru Bọ́ Lẹ́wọ̀n

6 Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na. 7 Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀. 8 Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. 9 On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran. 10 Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ. 11 Nigbati oju Peteru si walẹ, o ni, Nigbayi ni mo to mọ̀ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rẹ̀, o si gbà mi li ọwọ́ Herodu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju. 12 Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura. 13 Bi o si ti kàn ilẹkun ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin kan ti a npè ni Roda, o wá dahun. 14 Nigbati o si ti mọ̀ ohùn Peteru, kò ṣí ilẹkun fun ayọ̀, ṣugbọn o sure wọle, o si sọ pe, Peteru duro li ẹnu-ọ̀na. 15 Nwọn si wi fun u pe, Iwọ nṣiwère. Ṣugbọn o tẹnumọ́ ọ gidigidi pe Bẹ̃ni sẹ. Nwọn si wipe, Angẹli rẹ̀ ni. 16 Ṣugbọn Peteru nkànkun sibẹ, nigbati nwọn si ṣí ilẹkun, nwọn ri i, ẹnu si yà wọn. 17 Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran. 18 Nigbati ilẹ si mọ́, èmimì diẹ kọ li o wà lãrin awọn ọmọ-ogun pe, nibo ni Peteru gbé wà. 19 Nigbati Herodu si wá a kiri, ti kò si ri i, o wádi awọn ẹ̀ṣọ, o paṣẹ pe, ki a pa wọn. O si sọkalẹ lati Judea lọ si Kesarea, o si joko nibẹ̀.

Bí Hẹrọdu Ṣe Kú

20 Herodu si mbinu gidigidi si awọn ara Tire on Sidoni: ṣugbọn nwọn fi ọkàn kan wá sọdọ rẹ̀, nigbati nwọn si ti tu Blastu iwẹfa ọba loju, nwọn mbẹbẹ fun alafia; nitori lati ilu ọba lọ li a ti mbọ́ ilu wọn. 21 Lọjọ afiyesi kan, Herodu gunwà, o joko lori itẹ́, o si nsọ̀rọ fun wọn. 22 Awọn enia si hó, wipe, Ohùn ọlọrun ni, kì si iṣe ti enia. 23 Lojukanna angẹli Oluwa lù u, nitoriti kò fi ogo fun Ọlọrun: idin si jẹ ẹ, o si kú. 24 Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun gbilẹ, o si bi si i. 25 Barnaba on Saulu si pada ti Jerusalemu wá, nigbati nwọn si pari iṣẹ-iranṣẹ wọn, nwọn si mu Johanu wá pẹlu wọn, apele ẹniti ijẹ Marku.

Iṣe 13

A Yan Barnaba ati Saulu fún Iṣẹ́ Pataki

1 AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu. 2 Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si. 3 Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si rán wọn lọ.

Àwọn Òjíṣẹ́ Waasu ní Kipru

4 Njẹ bi a ti rán wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ lọ, nwọn sọkalẹ lọ si Seleukia; lati ibẹ̀ nwọn si wọkọ̀ lọ si Kipru. 5 Nigbati nwọn si wà ni Salami, nwọn nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni sinagogu awọn Ju: nwọn si ni Johanu pẹlu fun iranṣẹ wọn. 6 Nigbati nwọn si là gbogbo erekùṣu já de Pafo, nwọn ri ọkunrin kan, oṣó, woli eke, Ju, orukọ ẹniti ijẹ Barjesu, 7 Ẹniti o wà lọdọ Sergiu Paulu bãlẹ ilu na, amoye enia. On na li o ranṣẹ pè Barnaba on Saulu, o si fẹ gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun. 8 Ṣugbọn Elima oṣó na (nitori bẹ̃ni itumọ̀ orukọ rẹ̀) o takò wọn, o nfẹ pa bãlẹ ni ọkàn da kuro ni igbagbọ́. 9 Ṣugbọn Saulu (ti a si npè ni Paulu), o kún fun Ẹmí Mimọ́, o si tẹjumọ́ ọ, o si wipe, 10 Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po? 11 Njẹ nisisiyi, wo o, ọwọ́ Oluwa mbẹ lara rẹ, iwọ o si fọju, iwọ kì yio ri õrùn ni sã kan. Lojukanna owusuwusu ati òkunkun si bò o; o si nwá enia kiri lati fà a lọwọ lọ. 12 Nigbati bãlẹ ri ohun ti o ṣe, o gbagbọ́, ẹnu si yà a si ẹkọ́ Oluwa.

Paulu ati Barnaba Lọ sí Antioku Ilẹ̀ Pisidia

13 Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu. 14 Nigbati nwọn si là Perga kọja, nwọn wá si Antioku ni Pisidia, nwọn si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ isimi, nwọn si joko. 15 Ati lẹhin kìka iwe ofin ati iwe awọn woli, awọn olori sinagogu ranṣẹ si wọn, pe, Ará, bi ẹnyin ba li ọ̀rọ iyanju kan fun awọn enia, ẹ sọ ọ. 16 Paulu si dide duro, o si juwọ́ si wọn, o ni, Ẹnyin enia Israeli, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ẹ fi etí silẹ. 17 Ọlọrun awọn enia Israeli yi, yàn awọn baba wa, o si gbé awọn enia na leke, nigbati nwọn ṣe atipo ni ilẹ Egipti, apá giga li o si fi mu wọn jade kuro ninu rẹ̀. 18 Ni ìwọn igba ogoji ọdún li o fi mu sũru fun ìwa wọn ni ijù. 19 Nigbati o si ti run orilẹ-ède meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn ãdọta-le-ni-irinwo ọdun. 20 Ati lẹhin nkan wọnyi o fi onidajọ fun wọn, titi o fi di igba Samueli woli. 21 Ati lẹhinna ni nwọn bère ọba: Ọlọrun si fun wọn ni Saulu ọmọ Kiṣi, ọkunrin kan ninu ẹ̀ya Benjamini, fun ogoji ọdún. 22 Nigbati o si mu u kuro, o gbé Dafidi dide li ọba fun wọn; ẹniti o si jẹri rẹ̀ pe, Mo ri Dafidi ọmọ Jesse ẹni bi ọkàn mi, ti yio ṣe gbogbo ifẹ mi. 23 Lati inu iru-ọmọ ọkunrin yi ni Ọlọrun ti gbe Jesu Olugbala dide fun Israeli gẹgẹ bi ileri, 24 Nigbati Johanu ti kọ́ wãsu baptismu ironupiwada fun gbogbo enia Israeli ṣaju wíwa rẹ̀. 25 Bi Johanu si ti nlà ipa tirẹ̀ já, o ni, Tali ẹnyin ṣebi emi iṣe? Emi kì iṣe on. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ẹnikan mbọ̀ lẹhin mi, bata ẹsẹ ẹniti emi kò to itú. 26 Ará, ẹnyin ọmọ iran Abrahamu, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awa li a rán ọ̀rọ igbala yi si. 27 Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi. 28 Ati bi nwọn kò tilẹ ti ri ọ̀ran iku si i, sibẹ nwọn rọ̀ Pilatu lati pa a. 29 Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì. 30 Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú: 31 O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia. 32 Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba, 33 Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. 34 Ati niti pe o ji i dide kuro ninu oku, ẹniti kì yio tun pada si ibajẹ mọ́, o wi bayi pe, Emi ó fun nyin ni ore mimọ́ Dafidi, ti o daju. 35 Nitori o si wi ninu Psalmu miran pẹlu pe, Iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ri idibajẹ. 36 Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ. 37 Ṣugbọn ẹniti Ọlọrun ji dide kò ri idibajẹ. 38 Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin: 39 Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose. 40 Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe; 41 Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin. 42 Bi nwọn si ti njade, nwọn bẹ̀bẹ pe ki a sọ̀rọ wọnyi fun wọn li ọjọ isimi ti mbọ̀. 43 Nigbati nwọn si jade ni sinagogu, ọ̀pọ ninu awọn Ju ati ninu awọn olufọkansìn alawọṣe tẹle Paulu on Barnaba: awọn ẹniti o ba wọn sọ̀rọ ti nwọn si rọ̀ wọn lati duro ninu ore-ọfẹ Ọlọrun. 44 Li ọjọ isimi keji, gbogbo ilu si fẹrẹ pejọ tan lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun. 45 Ṣugbọn nigbati awọn Ju ri ọ̀pọ enia na, nwọn kún fun owu, nwọn nsọ̀rọ-òdi si ohun ti Paulu nsọ. 46 Paulu on Barnaba si sọ laibẹru pe, Ẹnyin li o tọ ki a kọ́ sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ sì kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi. 47 Bẹ̃li Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbé ọ kalẹ fun imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le jẹ fun igbala titi de opin aiye. 48 Nigbati awọn Keferi si gbọ́ eyi, nwọn yọ̀, nwọn si yìn ọ̀rọ Ọlọrun logo: gbogbo awọn ti a yàn si ìye ainipẹkun si gbagbọ́. 49 A si tàn ọ̀rọ Oluwa ka gbogbo ẹkùn na. 50 Ṣugbọn awọn Ju rú awọn obinrin olufọkansin ati ọlọlá soke ati awọn àgba ilu na, nwọn si gbe inunibini dide si Paulu on Barnaba, nwọn si ṣí wọn kuro li àgbegbe wọn. 51 Ṣugbọn nwọn gbọ̀n ekuru ẹsẹ wọn si wọn, nwọn si wá si Ikonioni. 52 Awọn ọmọ-ẹhin si kún fun ayọ̀ ati fun Ẹmí Mimọ́.

Iṣe 14

Iṣẹ́ Paulu ati Barnaba ní Ikonioni

1 O si ṣe, ni Ikonioni, nwọn jumọ wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ, nwọn si sọrọ tobẹ̃, ti ọ̀pọlọpọ awọn Ju ati awọn Hellene gbagbọ́. 2 Ṣugbọn awọn alaigbagbọ́ Ju rú ọkàn awọn Keferi soke, nwọn si rọ̀ wọn si awọn arakunrin na. 3 Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe. 4 Ṣugbọn ọ̀pọ enia ilu na pin meji: apakan si dàpọ mọ́ awọn Ju, apakan si dàpọ mọ́ awọn aposteli. 5 Bi awọn Keferi, ati awọn Ju pẹlu awọn olori wọn ti fẹ kọlù wọn lati ṣe àbuku si wọn, ati lati sọ wọn li okuta, 6 Nwọn mọ̀, nwọn si sá lọ si Listra ati Derbe ilu Likaonia, ati si àgbegbe ti o yiká: 7 Nibẹ̀ ni nwọn si nwasu ihinrere.

Iṣẹ́ Paulu ati Barnaba ní Listra

8 Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri. 9 Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada, 10 O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn. 11 Nigbati awọn enia si ri ohun ti Paulu ṣe, nwọn gbé ohùn wọn soke li ède Likaonia, wipe, Awọn oriṣa sọkalẹ tọ̀ wa wá ni àwọ enia. 12 Nwọn si pè Barnaba ni Jupiteri ati Paulu ni Herme nitori on li olori ọ̀rọ isọ. 13 Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia. 14 Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara. 15 Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn: 16 Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn. 17 Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin. 18 Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn. 19 Awọn Ju kan si ti Antioku ati Ikonioni wá, nigbati nwọn yi awọn enia li ọkàn pada, nwọn si sọ Paulu li okuta, nwọn wọ́ ọ jade kuro ni ilu na, nwọn ṣebi o kú. 20 Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin duro tì i yiká, o dide, o si wọ̀ ilu na lọ: ni ijọ keji o ba Barnaba lọ si Derbe. 21 Nigbati nwọn si ti wasu ihinrere fun ilu na, ti nwọn si ni ọmọ-ẹ̀hin pupọ, nwọn pada lọ si Listra, ati Ikonioni, ati si Antioku. 22 Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun. 23 Nigbati nwọn si ti yàn awọn àgbagba fun olukuluku ijọ, ti nwọn si ti fi àwẹ gbadura, nwọn fi wọn le Oluwa lọwọ, ẹniti nwọn gbagbọ́. 24 Nigbati nwọn si là Pisidia já, nwọn wá si Pamfilia. 25 Nigbati nwọn si ti sọ ọ̀rọ na ni Perga, nwọn sọkalẹ lọ si Atalia: 26 Ati lati ibẹ̀ lọ nwọn ba ti ọkọ̀ lọ si Antioku, lati ibiti a gbé ti fi wọn le õre-ọfẹ Ọlọrun lọwọ, fun iṣẹ ti nwọn ṣe pari. 27 Nigbati nwọn si de, ti nwọn si pè ijọ jọ, nwọn ròhin gbogbo ohun ti Ọlọrun fi wọn ṣe, ati bi o ti ṣí ilẹkun igbagbọ́ fun awọn Keferi. 28 Ki iṣe igba diẹ ni nwọn ba awọn ọmọ-ẹhin gbé.

Iṣe 15

Ìgbìmọ̀ Ìjọ Jerusalẹmu

1 AWỌN ọkunrin kan ti Judea sọkalẹ wá, nwọn si kọ́ awọn arakunrin pe, Bikoṣepe a ba kọ nyin ni ilà bi iṣe Mose, ẹnyin kì yio le là. 2 Nigbati iyapa ati iyàn jijà ti mbẹ lãrin Paulu on Barnaba kò si mọ ni ìwọn, awọn arakunrin yàn Paulu on Barnaba, ati awọn miran ninu wọn, ki nwọn goke lọ si Jerusalemu, sọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagba nitori ọ̀ran yi. 3 Nitorina nigbati ijọ si sìn wọn de ọna, nwọn là Fenike on Samaria kọja, nwọn nròhin iyipada awọn Keferi: nwọn si fi ayọ̀ nla fun gbogbo awọn arakunrin. 4 Nigbati nwọn si de Jerusalemu ijọ ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà tẹwọgba wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti Ọlọrun ti fi wọn ṣe. 5 Ṣugbọn awọn kan ti ẹya awọn Farisi ti nwọn gbagbọ́ dide, nwọn nwipe, a ni lati kọ wọn ni ilà, ati lati paṣẹ fun wọn pe ki nwọn ki o mã pa ofin Mose mọ́. 6 Ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà pejọ lati gbìmọ ọ̀ran yi. 7 Nigbati iyàn si di pipọ, Peteru dide, o si wi fun wọn pe, Ará, ẹnyin mọ̀ pe, lati ibẹrẹ Ọlọrun ti yàn ninu nyin, ki awọn Keferi ki o le gbọ́ ọ̀rọ ihinrere li ẹnu mi, ki nwọn si gbagbọ́. 8 Ati Ọlọrun, ti iṣe olumọ-ọkàn, o jẹ wọn li ẹrí, o nfun wọn li Ẹmí Mimọ́, gẹgẹ bi awa: 9 Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́. 10 Njẹ nitorina ẽṣe ti ẹnyin o fi dán Ọlọrun wò, lati fi àjaga bọ̀ awọn ọmọ-ẹhin li ọrùn, eyiti awọn baba wa ati awa kò le rù? 11 Ṣugbọn awa gbagbọ́ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa ó là, gẹgẹ bi awọn. 12 Gbogbo ajọ si dakẹ, nwọn si fi eti si Barnaba on Paulu, ti nwọn nròhin iṣẹ aṣẹ ati iṣẹ àmi ti Ọlọrun ti ti ọwọ́ wọn ṣe lãrin awọn Keferi. 13 Lẹhin ti nwọn si dakẹ, Jakọbu dahùn, wipe, Ará, ẹ gbọ ti emi: 14 Simeoni ti rohin bi Ọlọrun li akọṣe ti bojuwò awọn Keferi, lati yàn enia ninu wọn fun orukọ rẹ̀. 15 Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe, 16 Lẹhin nkan wọnyi li emi o pada, emi o si tún agọ́ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ; emi ó si tún ahoro rẹ̀ kọ́, emi ó si gbé e ró: 17 Ki awọn enia iyokù le mã wá Oluwa, ati gbogbo awọn Keferi lara ẹniti a npè orukọ mi, 18 Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa. 19 Njẹ ìmọràn temi ni, ki a máṣe yọ awọn ti o yipada si Ọlọrun lẹnu ninu awọn Keferi: 20 Ṣugbọn ki a kọwe si wọn, ki nwọn ki o fà sẹhin kuro ninu ẽri oriṣa, ati kuro ninu àgbere, ati kuro ninu ohun ilọlọrun-pa, ati kuro ninu ẹ̀jẹ. 21 Mose nigba atijọ sa ní awọn ti nwasu rẹ̀ ni ilu gbogbo, a ma kà a ninu sinagogu li ọjọjọ isimi.

Ìpinnu ìgbìmọ̀

22 Nigbana li o tọ́ loju awọn aposteli, ati awọn àgbagbà pẹlu gbogbo ijọ, lati yàn enia ninu wọn, ati lati ran wọn lọ si Antioku pẹlu Paulu on Barnaba: Juda ti a npè apele rẹ̀ ni Barsaba, ati Sila, ẹniti o l'orukọ ninu awọn arakunrin. 23 Nwọn si kọ iwe le wọn lọwọ bayi pe, Awọn aposteli, ati awọn àgbagbà, ati awọn arakunrin, kí awọn arakunrin ti o wà ni Antioku, ati ni Siria, ati ni Kilikia ninu awọn Keferi: 24 Niwọnbi awa ti gbọ́ pe, awọn kan ti o ti ọdọ wa jade lọ fi ọ̀rọ yọ nyin li ẹnu, ti nwọn nyi nyin li ọkàn po, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣaima kọ ilà, ati ṣaima pa ofin Mose mọ́: ẹniti awa kò fun li aṣẹ: 25 O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn olufẹ wa. 26 Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi. 27 Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọ̀rọ ẹnu sọ ohun kanna fun nyin. 28 Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ: 29 Ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹ̀jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ́ kuro, ẹnyin ó ṣe rere. Alafia. 30 Njẹ nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn sọkalẹ wá si Antioku: nigbati nwọn si pè apejọ, nwọn fi iwe na fun wọn. 31 Nigbati nwọn si kà a, nwọn yọ̀ fun itunu na. 32 Bi Juda on Sila tikarawọn ti jẹ woli pẹlu, nwọn fi ọ̀rọ pipọ gbà awọn arakunrin niyanju, nwọn si mu wọn li ọkàn le. 33 Nigbati nwọn si pẹ diẹ, awọn arakunrin jọwọ wọn lọwọ lọ li alafia si ọdọ awọn ti o ran wọn. 34 Ṣugbọn o wù Sila lati gbé ibẹ̀. 35 Paulu on Barnaba si duro diẹ ni Antioku, nwọn nkọ́ni, nwọn si nwasu ọ̀rọ Oluwa, ati awọn pipọ miran pẹlu wọn.

Paulu ati Barnaba Gba Ọ̀nà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

36 Lẹhin ijọ melokan, Paulu si sọ fun Barnaba pe, Jẹ ki a tún pada lọ íbẹ awọn arakunrin wa wò, bi nwọn ti nṣe, ni ilu gbogbo ti awa ti wasu ọ̀rọ Oluwa. 37 Barnaba si pinnu rẹ̀ lati mu Johanu lọ pẹlu wọn, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Marku. 38 Ṣugbọn Paulu rò pe, kò yẹ lati mu u lọ pẹlu wọn, ẹniti o fi wọn silẹ ni Pamfilia, ti kò si ba wọn lọ si iṣẹ na. 39 Ìja na si pọ̀ tobẹ̃, ti nwọn yà ara wọn si meji: nigbati Barnaba si mu Marku, o ba ti ọkọ̀ lọ si Kipru; 40 Ṣugbọn Paulu yàn Sila, o si lọ, bi a ti fi i lé ore-ọfẹ Oluwa lọwọ lati ọdọ awọn arakunrin. 41 O si là Siria on Kilikia lọ, o nmu ijọ li ọkàn le.

Iṣe 16

Timotiu ba Paulu ati Sila lọ

1 O si wá si Derbe on Listra: si kiyesi i, ọmọ-ẹhin kan wà nibẹ̀, ti a npè ni Timotiu, ọmọ obinrin kan ti iṣe Ju, ti o gbagbọ́; ṣugbọn Hellene ni baba rẹ̀: 2 Ẹniti a rohin rẹ̀ rere lọdọ awọn arakunrin ti o wà ni Listra ati Ikonioni. 3 On ni Paulu fẹ ki o ba on lọ; o si mu u, o si kọ ọ ni ilà, nitori awọn Ju ti o wà li àgbegbe wọnni: nitori gbogbo wọn mọ̀ pe, Hellene ni baba rẹ̀. 4 Bi nwọn si ti nlà awọn ilu lọ, nwọn nfi awọn aṣẹ ti a ti pinnu le wọn lọwọ lati mã pa wọn mọ, lati ọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagbà wá ti o wà ni Jerusalemu. 5 Bẹ̃ni awọn ijọ si fẹsẹmulẹ ni igbagbọ́, nwọn si npọ̀ si i ni iye lojojumọ.

Paulu Rí Ará Makedonia Kan ní Ojú Ìran

6 Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́ kọ̀ fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia. 7 Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn. 8 Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi. 9 Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ. 10 Nigbati o si ti ri iran na, lọgán awa mura lati lọ si Makedonia, a si gbà pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn.

Lidia di Onigbagbọ

11 Nitorina nigbati awa ṣikọ̀ ni Troasi a ba ọ̀na tàra lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli; 12 Lati ibẹ̀ awa si lọ si Filippi, ti iṣe ilu Makedonia, olu ilu ìha ibẹ, ilu labẹ Romani: awa si joko ni ilu yi fun ijọ melokan. 13 Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ. 14 Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ. 15 Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.

Wọ́n Juu Paulu ati Sila Sẹ́wọ̀n ní Filipi

16 O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá: 17 On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin. 18 O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna. 19 Nigbati awọn oluwa rẹ̀ si ri pe, igbẹkẹle ère wọn pin, nwọn mu Paulu on Sila, nwọn si wọ́ wọn lọ si ọjà tọ̀ awọn ijoye lọ; 20 Nigbati nwọn si mu wọn tọ̀ awọn onidajọ lọ, nwọn wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ti iṣe Ju, nwọn nyọ ilu wa lẹnu jọjọ; 21 Nwọn si nkọni li àṣa ti kò yẹ fun wa, awa ẹniti iṣe ara Romu, lati gbà, ati lati tẹle. 22 Ọpọ enia si jumọ dide si wọn: awọn olori si fà wọn li aṣọ ya, nwọn si paṣẹ pe, ki a fi ọgọ lù wọn. 23 Nigbati nwọn si lù wọn pupọ, nwọn sọ wọn sinu tubu, nwọn kìlọ fun onitubu ki o pa wọn mọ́ daradara: 24 Nigbati o gbọ́ irú ikilọ bẹ̃, o sọ wọn sinu tubu ti inu lọhun, o si kàn ãbà mọ wọn li ẹsẹ. 25 Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn. 26 Lojiji iṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, tobẹ̃ ti ipilẹ ile tubu mi titi: lọgan gbogbo ilẹkun si ṣí, ìde gbogbo wọn si tu silẹ. 27 Nigbati onitubu si tají, ti o si ri pe, awọn ikẹkun tubu ti ṣí silẹ, o fà idà rẹ̀ yọ, o si fẹ pa ara rẹ̀, o ṣebi awọn ara tubu ti sá lọ. 28 Ṣugbọn Paulu kọ kàrá, wipe, Máṣe pa ara rẹ lara: nitori gbogbo wa mbẹ nihinyi. 29 Nigbati o si bere iná, o bẹ́ sinu ile, o nwariri, o wolẹ niwaju Paulu on Sila. 30 O si mu wọn jade, o ni, Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là? 31 Nwọn si wi fun u pe, Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu. 32 Nwọn si sọ ọ̀rọ Oluwa fun u, ati fun gbogbo awọn ará ile rẹ̀. 33 O si mu wọn ni wakati na li oru, o wẹ̀ ọgbẹ wọn; a si baptisi rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀ lojukanna. 34 O si mu wọn wá si ile rẹ̀, o si gbé onjẹ kalẹ niwaju wọn, o si yọ̀ gidigidi pẹlu gbogbo awọn ará ile rẹ̀, nitori o gbà Ọlọrun gbọ. 35 Ṣugbọn nigbati ilẹ mọ́, awọn onidajọ rán awọn ọlọpa pe, Da awọn enia wọnni silẹ. 36 Onitubu si sọ ọrọ na fun Paulu, wipe, Awọn onidajọ ranṣẹ pe ki a dá nyin silẹ: njẹ nisisiyi ẹ jade ki ẹ si mã lọ li alafia. 37 Ṣugbọn Paulu wi fun wọn pe, Nwọn lù wa ni gbangba, nwọn si sọ wa sinu tubu li aijẹbi, awa ẹniti iṣe ara Romu: nisisiyi nwọn si fẹ ti wa jade nikọ̀kọ? agbẹdọ; ṣugbọn ki awọn tikarawọn wá mu wa jade. 38 Awọn ọlọpa si sọ ọrọ wọnyi fun awọn onidajọ: ẹ̀ru si bà wọn, nigbati nwọn gbọ́ pe ara Romu ni nwọn. 39 Nwọn si wá, nwọn ṣìpẹ fun wọn, nwọn si mu wọn jade, nwọn si bẹ̀ wọn pe, ki nwọn ki o jade kuro ni ilu na. 40 Nwọn si jade ninu tubu, nwọn si wọ̀ ile Lidia lọ: nigbati nwọn si ti ri awọn arakunrin, nwọn tù wọn ninu, nwọn si jade kuro.

Iṣe 17

Ìdàrúdàpọ̀ ní Tẹssalonika

1 NIGBATI nwọn si ti kọja Amfipoli ati Apollonia, nwọn wá si Tessalonika, nibiti sinagogu awọn Ju wà: 2 Ati Paulu, gẹgẹbi iṣe rẹ̀, o wọle tọ̀ wọn lọ, li ọjọ isimi mẹta o si mba wọn fi ọ̀rọ we ọ̀rọ ninu iwe-mimọ́, 3 O ntumọ, o si nfihàn pe, Kristi kò le ṣaima jìya, ki o si jinde kuro ninu okú; ati pe, Jesu yi, ẹniti emi nwasu fun nyin, on ni Kristi na. 4 A si yi ninu wọn lọkàn pada, nwọn si darapọ̀ mọ́ Paulu on Sila; ati ninu awọn olufọkansìn Hellene ọ̀pọ pupọ, ati ninu awọn obinrin ọlọlá, kì iṣe diẹ. 5 Ṣugbọn awọn Ju jowu, nwọn si fà awọn jagidijagan ninu awọn ijajẹ enia mọra, nwọn gbá ẹgbẹ jọ, nwọn si nrú ilu; nwọn si kọlù ile Jasoni, nwọn nfẹ mu wọn jade tọ̀ awọn enia wá. 6 Nigbati nwọn kò si ri wọn, nwọn wọ́ Jasoni, ati awọn arakunrin kan tọ̀ awọn olori ilu lọ, nwọn nkigbe pe, Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi pẹlu; 7 Awọn ẹniti Jasoni gbà si ọdọ: gbogbo awọn wọnyi li o si nhuwa lodi si aṣẹ Kesari, wipe, ọba miran kan wà, Jesu. 8 Awọn enia ati awọn olori ilu kò ni ibalẹ aiya nigbati nwọn gbọ́ nkan wọnyi. 9 Nigbati nwọn si gbà ogò lọwọ Jasoni ati awọn iyokù, nwọn jọwọ lọ.

Paulu ati Sila lọ sí Berea

10 Lọgan awọn arakunrin si rán Paulu on Sila lọ si Berea li oru: nigbati nwọn si de ibẹ̀, nwọn wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ. 11 Awọn wọnyi si ni iyìn jù awọn ti Tessalonika lọ, niti pe nwọn fi tọkantọkan gbà ọ̀rọ na, nwọn si nwá inu iwe-mimọ́ lojojumọ́ bi nkan wọnyi ri bẹ̃. 12 Nitorina pipọ ninu wọn gbagbọ́; ati ninu awọn obinrin Hellene ọlọlá, ati ninu awọn ọkunrin, kì iṣe diẹ. 13 Ṣugbọn nigbati awọn Ju ti Tessalonika mọ̀ pe, Paulu nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni Berea, nwọn si wá sibẹ̀ pẹlu, nwọn rú awọn enia soke. 14 Nigbana li awọn arakunrin rán Paulu jade lọgan lati lọ titi de okun: Ṣugbọn Sila on Timotiu duro sibẹ̀. 15 Awọn ti o sin Paulu wá si mu u lọ titi de Ateni; nigbati nwọn si gbà aṣẹ lọdọ rẹ̀ tọ̀ Sila on Timotiu wá pe, ki nwọn ki o yára tọ̀ on wá, nwọn lọ.

Paulu ní Atẹni

16 Nigbati Paulu duro dè wọn ni Ateni, ọkàn rẹ̀ rú ninu rẹ̀, nigbati o ri pe ilu na kún fun oriṣa. 17 Nitorina o mba awọn Ju fi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀ ninu sinagogu, ati awọn olufọkansin, ati awọn ti o mba pade lọja lojojumọ. 18 Ninu awọn Epikurei pẹlu, ati awọn ọjọgbọ́n Stoiki kótì i. Awọn kan si nwipe, Kili alahesọ yi yio ri wi? awọn miran si wipe, O dabi oniwasu ajeji oriṣa: nitoriti o nwasu Jesu, on ajinde fun wọn. 19 Nwọn si mu u, nwọn si fà a lọ si Areopagu, nwọn wipe, A ha le mọ̀ kili ẹkọ́ titun ti iwọ nsọrọ rẹ̀ yi jẹ́. 20 Nitoriti iwọ mu ohun ajeji wá si etí wa: awa si nfẹ mọ̀ kini itumọ nkan wọnyi. 21 Nitori gbogbo awọn ará Ateni, ati awọn alejò ti nṣe atipo nibẹ kì iṣe ohun miran jù, ki a mã sọ tabi ki a ma gbọ́ ohun titun lọ. 22 Paulu si dide duro larin Areopagu, o ni, Ẹnyin ará Ateni, mo woye pe li ohun gbogbo ẹ kun fun oniruru isin ju. 23 Nitori bi mo ti nkọja lọ, ti mo wò ohun wọnni ti ẹnyin nsìn, mo si ri pẹpẹ kan ti a kọ akọle yi si, FUN ỌLỌRUN AIMỌ̀. Njẹ ẹniti ẹnyin nsìn li aimọ̀ on na li emi nsọ fun nyin. 24 Ọlọrun na ti o da aiye ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, on na ti iṣe Oluwa ọrun on aiye, kì igbé ile ti a fi ọwọ́ kọ́; 25 Bẹ̃ni a kì ifi ọwọ́ enia sìn i, bi ẹnipe o nfẹ nkan, on li o fi ìye ati ẽmi ati ohun gbogbo fun gbogbo enia, 26 O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn; 27 Ki nwọn ki o le mã wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn ba le fà si i, ti wọn si ri i, bi o tilẹ ṣe pe kò jina si olukuluku wa: 28 Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀. 29 Njẹ bi awa ba ṣe ọmọ Ọlọrun, kò yẹ fun wa ki a rò pe, Iwa-Ọlọrun dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọ́n ati ihumọ enia ṣe li ọnà. 30 Pẹlupẹlu igba aimọ̀ yi li Ọlọrun ti foju fò da; ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada: 31 Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú. 32 Nigbati nwọn ti gbọ́ ti ajinde okú, awọn miran nṣẹ̀fẹ: ṣugbọn awọn miran wipe, Awa o tún nkan yi gbọ́ li ẹnu rẹ. 33 Bẹ̃ni Paulu si jade kuro larin wọn. 34 Ṣugbọn awọn ọkunrin kan fi ara mọ́ ọ, nwọn si gbagbọ́: ninu awọn ẹniti Dionisiu ara Areopagu wà, ati obinrin kan ti a npè ni Damari, ati awọn miran pẹlu wọn.

Iṣe 18

Iṣẹ́ Paulu ní Kọrinti

1 LẸHIN nkan wọnyi, Paulu jade kuro ni Ateni, o si lọ si Korinti; 2 O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá. 3 Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn. 4 O si nfọ̀rọ̀ we ọrọ fun wọn ninu sinagogu li ọjọjọ isimi, o si nyi awọn Ju ati awọn Hellene li ọkàn pada. 5 Nigbati Sila on Timotiu si ti Makedonia wá, ọrọ na ká Paulu lara, o nfi hàn, o sọ fun awọn Ju pe, Jesu ni Kristi na. 6 Nigbati nwọn si wà li òdi, ti nwọn si nsọrọ-odi, o gbọ̀n aṣọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ̀jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ́: lati isisiyi lọ emi o tọ̀ awọn Keferi lọ. 7 O si lọ kuro nibẹ̀, o wọ̀ ile ọkunrin kan ti a npè ni Titu Justu, ẹniti o nsìn Ọlọrun ti ile rẹ̀ fi ara mọ́ sinagogu tímọ́tímọ́. 8 Ati Krispu, olori sinagogu, o gbà Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ile rẹ̀; ati ọ̀pọ ninu awọn ara Korinti, nigbati nwọn gbọ́, nwọn gbagbọ́, a si baptisi wọn. 9 Oluwa si sọ fun Paulu li oru li ojuran pe, Má bẹ̀ru, sá mã sọ, má si ṣe pa ẹnu rẹ mọ́: 10 Nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pipọ ni ilu yi. 11 O si joko nibẹ̀ li ọdún kan on oṣù mẹfa, o nkọ́ni li ọ̀rọ Ọlọrun lãrin wọn.

Ọlọrun Láàrin Wọn.

12 Nigbati Gallioni si jẹ bãlẹ Akaia, awọn Ju fi ọkàn kan dide si Paulu, nwọn si mu u wá siwaju itẹ idajọ. 13 Nwọn wipe, ọkunrin yi nyi awọn enia li ọkàn pada, lati mã sin Ọlọrun lodi si ofin. 14 Nigbati Paulu nfẹ ati dahùn, Gallioni wi fun awọn Ju pe, Ibaṣepe ọ̀ran buburu tabi ti jagidijagan kan ni, bi ọ̀rọ ti ri, ẹnyin Ju, emi iba gbè nyin: 15 Ṣugbọn bi o ba ṣe ọ̀ran nipa ọ̀rọ ati orukọ, ati ti ofin nyin ni, ki ẹnyin ki o bojuto o fun ara nyin, nitoriti emi kò fẹ ṣe onidajọ nkan bawọnni. 16 O si lé wọn kuro ni ibi itẹ idajọ. 17 Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi.

Paulu Pada Lọ sí Antioku

18 Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ. 19 O si sọkalẹ wá si Efesu, o si fi wọn silẹ nibẹ̀: ṣugbọn on tikararẹ̀ wọ̀ inu sinagogu lọ, o si ba awọn Ju fi ọrọ we ọrọ. 20 Nigbati nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o ba awọn joko diẹ si i, o kọ̀; 21 Ṣugbọn o dágbere fun wọn, o si wipe, Emi kò gbọdọ ṣaima ṣe ajọ ọdún ti mbọ̀ yi ni Jerusalemu bi o ti wù ki o ri: ṣugbọn emi ó tún pada tọ̀ nyin wá, bi Ọlọrun ba fẹ. O si ṣikọ̀ ni Efesu. 22 Nigbati o si ti gúnlẹ ni Kesarea, ti o goke, ti o si ki ijọ, o sọkalẹ lọ si Antioku. 23 Nigbati o si gbé ọjọ diẹ nibẹ̀, o lọ, o si kọja ni ilẹ Galatia on Frigia lẹsẹsẹ, o nmu gbogbo awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le.

Apolo Dé Efesu

24 Ju kan si wà ti a npè ni Apollo, ti a bí ni Aleksandria, ọkunrin ọlọrọ li ẹnu, ti o pọ̀ ni iwe-mimọ́, o wá si Efesu. 25 Ọkunrin yi li a ti kọ́ ni ọ̀na ti Oluwa; o si ṣe ẹniti o gboná li ọkàn, o nfi ãyan nsọ̀rọ, o si nkọ́ni ni nkan ti Oluwa; kìki baptismu ti Johanu li o mọ̀. 26 O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju. 27 Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ. 28 Nitoriti o sọ asọye fun awọn Ju ni gbangba, o nfi i hàn ninu iwe-mimọ́ pe, Jesu ni Kristi.

Iṣe 19

Paulu Dé Efesu

1 O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan; 2 O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà. 3 O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu. 4 Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu. 5 Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa. 6 Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ. 7 Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila. 8 Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun. 9 Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu. 10 Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene.

Àwọn Ọmọ Skefa

11 Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe, 12 Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn. 13 Ṣugbọn awọn Ju kan alarinkiri, alẹmi-èṣu-jade, dawọle e li adabọwọ ara wọn, lati pè orukọ Jesu Oluwa si awọn ti o li ẹmi buburu, wipe, Awa fi orukọ Jesu ti Paulu nwasu fi nyin bu. 14 Awọn meje kan si wà, ọmọ ẹnikan ti a npè ni Skefa, Ju, ati olori kan ninu awọn alufa, ti nwọn ṣe bẹ̃. 15 Ẹmi buburu na si dahùn, o ni, Jesu emi mọ̀, Paulu emi si mọ̀; ṣugbọn tali ẹnyin? 16 Nigbati ọkunrin ti ẹmi buburu wà lara rẹ̀ si fò mọ́ wọn, o ba wọn dimú, o bori wọn, bẹ̃ni nwọn sá jade kuro ni ile na ni ìhoho ati ni ifarapa. 17 Ihìn yi si di mimọ̀ fun gbogbo awọn Ju ati awọn ara Hellene pẹlu ti o ṣe atipo ni Efesu; ẹ̀ru si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu Oluwa ga. 18 Ọ̀pọ awọn ti nwọn gbagbọ́ si wá, nwọn jẹwọ, nwọn si fi iṣẹ wọn hàn. 19 Kì isi ṣe diẹ ninu awọn ti nṣe àlúpàyídà li o kó iwe wọn jọ, nwọn dáná sun wọn loju gbogbo enia: nwọn si ṣírò iye wọn, nwọn si ri i, o jẹ ẹgbã-mẹdọgbọ̀n iwọn fadaka. 20 Bẹ̃li ọ̀rọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ.

Ìrúkèrúdò Bẹ́ Sílẹ̀ ní Efesu

21 Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu. 22 Nigbati o si ti rán meji ninu awọn ti nṣe iranṣẹ fun u lọ si Makedonia, Timotiu ati Erastu, on tikararẹ̀ duro ni Asia ni igba diẹ na. 23 Li akokò na èmìmì diẹ ki o wà nitori Ọna na. 24 Nitori ọkunrin kan ti a npè ni Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ti ima fi fadaka ṣe ile-oriṣa fun Diana, o mu ère ti kò mọ̀ ni iwọn fun awọn oniṣọnà wá; 25 Nigbati o pè wọn jọ, ati irú awọn ọlọnà bẹ̃, o ni, Alàgba, ẹnyin mọ̀ pe nipa iṣẹ-ọna yi li awa fi li ọrọ̀ wa. 26 Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun. 27 Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ. 28 Nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn kún fun ibinu, nwọn kigbe, wipe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. 29 Gbogbo ilu na si kún fun irukerudò: nwọn fi ọkàn kan rọ́ sinu ile ibĩṣire, nwọn si mu Gaiu ati Aristarku ara Makedonia, awọn ẹgbẹ ajọrin Paulu. 30 Nigbati Paulu si nfẹ wọ̀ ãrin awọn enia lọ, awọn ọmọ-ẹhin kò jẹ fun u. 31 Awọn olori kan ara Asia, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ranṣẹ si i, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe fi ara rẹ̀ wewu ninu ile ibiṣire. 32 Njẹ awọn kan nwi ohun kan, awọn miran nwi omiran: nitori ajọ di rudurudu; ati ọ̀pọ enia ni kò mọ̀ itori ohun ti nwọn tilẹ fi wọjọ pọ̀ si. 33 Nwọn si fà Aleksanderu kuro li awujọ, awọn Ju tì i ṣaju. Aleksanderu si juwọ́ si wọn, on iba si wi ti ẹnu rẹ̀ fun awọn enia. 34 Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. 35 Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ? 36 Njẹ bi a ko ti le sọrọ odi si nkan wọnni, o yẹ ki ẹ dakẹ, ki ẹnyin ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun. 37 Nitoriti ẹnyin mu awọn ọkunrin wọnyi wá, nwọn kò kó ile oriṣa, bẹ̃ni nwọn kò sọrọ-odi si oriṣa wa. 38 Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn. 39 Ṣugbọn bi ẹ ba nwadi ohun kan nipa ọ̀ran miran, a ó pari rẹ̀ ni ajọ ti o tọ́. 40 Nitori awa sá wà li ewu ati pè bi lẽrè nitori ariwo oni yi, kò sa nidi, ati nitori eyi awa kì yio le dahun fun iwọjọ yi. 41 Nigbati o si ti sọ bẹ̃ tan, o tú ijọ na ká.

Iṣe 20

Paulu lọ sí Masedonia ati Ilẹ̀ Hellene

1 NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia. 2 Nigbati o si ti là apa ìha wọnni kọja, ti o si ti fi ọ̀rọ pipọ gbà wọn ni iyanju, o wá si ilẹ Hellene. 3 Nigbati o si duro nibẹ̀ li oṣù mẹta, ti awọn Ju si dèna dè e, bi o ti npete ati ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, o pinnu rẹ̀ lati ba ti Makedonia pada lọ. 4 Sopateru ara Berea ọmọ Parru si ba a lọ de Asia; ati ninu awọn ara Tessalonika, Aristarku on Sekundu; ati Gaiu ara Derbe, ati Timotiu; ati ara Asia, Tikiku on Trofimu. 5 Ṣugbọn awọn wọnyi ti lọ ṣiwaju, nwọn nduro dè wa ni Troa. 6 Awa si ṣikọ̀ lati Filippi wá lẹhin ọjọ aiwukara, a si de ọdọ wọn ni Troasi ni ijọ karun; nibiti awa gbé duro ni ijọ meje.

Paulu Bẹ Troasi Wò fún Ìgbà Ìkẹhìn

7 Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ. 8 Fitilà pipọ si wà ni yàrá oke na, nibiti a gbé pejọ si. 9 Ọdọmọkunrin kan ti a npè ni Eutiku si joko li oju ferese, orun si wọ̀ ọ lara: bi Paulu si ti pẹ ni iwasu, o ta gbọ́ngbọ́n loju orun, o ṣubu lati oke kẹta wá silẹ, a si gbé e dide li okú. 10 Nigbati Paulu si sọkalẹ, o wolẹ bò o, o gbá a mọra, o ni, Ẹ má yọ ara nyin lẹnu; nitori ẹmí rẹ̀ mbẹ ninu rẹ̀. 11 Nigbati o si tún gòke lọ, ti o si bù akara, ti o si jẹ, ti o si sọ̀rọ pẹ titi o fi di afẹmọjumọ́, bẹ̃li o lọ. 12 Nwọn si mu ọmọkunrin na bọ̀ lãye, inu nwọn si dun gidigidi.

Ìrìn Àjò láti Troasi Dé Miletu

13 Nigbati awa si ṣaju, awa si ṣikọ̀ lọ si Asso, nibẹ̀ li a nfẹ gbà Paulu si ọkọ̀: nitori bẹ̃li o ti pinnu rẹ̀, on tikararẹ̀ nfẹ ba ti ẹsẹ lọ. 14 Nigbati o pade wa ni Asso, ti a si ti gbà a si ọkọ̀, a lọ si Mitilene. 15 Nigbati a si ṣikọ̀ nibẹ̀, ni ijọ keji a de ọkankan Kio; ni ijọ keji rẹ̀ a de Samo, a si duro ni Trogillioni; ni ijọ keji rẹ̀ a si de Miletu. 16 Paulu sá ti pinnu rẹ̀ lati mu ọkọ̀ lọ niha Efesu, nitori ki o ma ba fi igba na joko ni Asia: nitori o nyára bi yio ṣe iṣe fun u, lati wà ni Jerusalemu li ọjọ Pentikosti.

Paulu Bá Àwọn Alàgbà Efesu Sọ̀rọ̀

17 Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀. 18 Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na, 19 Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju: 20 Bi emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣ'anfani fun nyin, ati lati mã kọ́ nyin ni gbangba ati lati ile de ile, 21 Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa. 22 Njẹ nisisiyi, wo o, ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalemu, laimọ̀ ohun ti yio bá mi nibẹ̀: 23 Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi. 24 Ṣugbọn emi kò kà ẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ̀ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati mã ròhin ihinrere ore-ọfẹ Ọlọrun. 25 Njẹ nisisiyi, wo o, emi mọ̀ pe gbogbo nyin, lãrin ẹniti emi ti nkiri wãsu ijọba Ọlọrun, kì yio ri oju mi mọ́. 26 Nitorina mo pè nyin ṣe ẹlẹri loni yi pe, ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia gbogbo. 27 Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin. 28 Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà. 29 Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si. 30 Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn. 31 Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru. 32 Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́. 33 Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni. 34 Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi. 35 Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ. 36 Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura. 37 Gbogbo wọn si sọkun gidigidi, nwọn si rọ̀ mọ́ Paulu li ọrùn, nwọn si fi ẹnu kò o li ẹnu, 38 Inu wọn si bajẹ julọ fun ọ̀rọ ti o sọ pe, nwọn kì yio ri oju on mọ́. Nwọn si sìn i lọ sinu ọkọ̀.

Iṣe 21

Ìrìn Àjò Paulu sí Jerusalẹmu

1 O si ṣe, nigbati awa kuro lọdọ wọn, ti a sì ṣikọ̀, awa ba ọ̀na tàra wá si Kosi, ni ijọ keji a si lọ si Rodu, ati lati ibẹ̀ lọ si Patara: 2 Nigbati awa si ri ọkọ̀ kan ti nrekọja lọ si Fenike, awa wọ̀ ọkọ̀, a si ṣí. 3 Nigbati awa si ti ri Kipru li òkere, ti awa fi i si ọwọ́ òsi, awa gbé ori ọkọ̀ le Siria, a si gúnlẹ ni Tire: nitori nibẹ̀ li ọkọ̀ yio gbé kó ẹrù silẹ. 4 Nigbati a si ri awọn ọmọ-ẹhin, awa duro nibẹ̀ ni ijọ meje: awọn ẹniti o tipa Ẹmí wi fun Paulu pe, ki o máṣe lọ si Jerusalemu. 5 Nigbati a si ti lò ọjọ wọnni tan, awa jade, a si mu ọ̀na wa pọ̀n; gbogbo nwọn si sìn wa, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọde titi awa fi jade si ẹhin ilu: nigbati awa si gunlẹ li ebute, awa si gbadura. 6 Nigbati a si ti dágbere fun ara wa, awa bọ́ si ọkọ̀; ṣugbọn awọn si pada lọ si ile wọn. 7 Nigbati a si ti pari àjo wa lati Tire, awa de Ptolemai; nigbati a si kí awọn ará, awa si ba wọn gbé ni ijọ kan. 8 Ni ijọ keji awa lọ kuro, a si wá si Kesarea: nigbati awa si wọ̀ ile Filippi Efangelisti, ọkan ninu awọn meje nì; awa si wọ̀ sọdọ rẹ̀. 9 Ọkunrin yi si li ọmọbinrin mẹrin, wundia, ti ima sọtẹlẹ. 10 Bi a si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, woli kan ti Judea sọkalẹ wá, ti a npè ni Agabu. 11 Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀ li ọwọ́ on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́ wi, Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ. 12 Nigbati a si ti gbọ́ nkan wọnyi, ati awa, ati awọn ará ibẹ̀ na bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe gòke lọ si Jerusalemu. 13 Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ ba ọkàn mi; nitori emi mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa. 14 Nigbati a kò le pa a li ọkàn dà, awa dakẹ, wipe, Ifẹ ti Oluwa ni ki a ṣe. 15 Lẹhin ijọ wọnni, awa palẹmọ, a si gòke lọ si Jerusalemu. 16 Ninu awọn ọmọ-ẹhin lati Kesarea ba wa lọ, nwọn si mu Mnasoni ọmọ-ẹhin lailai kan pẹlu wọn, ará Kipru, lọdọ ẹniti awa ó gbé wọ̀.

Paulu Lọ Bẹ Jakọbu Wò

17 Nigbati awa si de Jerusalemu, awọn arakunrin si fi ayọ̀ gbà wa. 18 Ni ijọ keji awa ba Paulu lọ sọdọ Jakọbu; gbogbo awọn alàgba si wà nibẹ̀. 19 Nigbati o si kí wọn tan, o ròhin ohun gbogbo lẹsẹsẹ ti Ọlọrun ṣe lãrin awọn Keferi nipa iṣẹ-iranṣẹ rẹ̀. 20 Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yin Ọlọrun logo, nwọn si wi fun u pe, Arakunrin, iwọ ri iye ẹgbẹgbẹrun ninu awọn Ju ti o gbagbọ, gbogbo nwọn li o si ni itara fun ofin. 21 Nwọn si ti ròhin rẹ fun wọn pe, Iwọ nkọ́ gbogbo awọn Ju ti o wà lãrin awọn Keferi pe, ki nwọn ki o kọ̀ Mose silẹ, o si nwi fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe kọ awọn ọmọ wọn ni ilà mọ́, ati ki nwọn ki o máṣe rìn gẹgẹ bi àṣa wọn. 22 Njẹ ewo ni ṣiṣe? ijọ kò le ṣaima pejọ pọ̀: dajudaju nwọn ó gbọ́ pe, iwọ de. 23 Njẹ eyi ti awa ó wi fun ọ yi ni ki o ṣe: Awa li ọkunrin mẹrin ti nwọn ni ẹ̀jẹ́ lara wọn; 24 Awọn ni ki iwọ ki o mu, ki o si ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn ki o si ṣe inawo wọn, ki nwọn ki o le fá ori wọn: gbogbo enia yio si mọ̀ pe, kò si otitọ kan ninu ohun ti nwọn gbọ si ọ; ṣugbọn pe, iwọ tikararẹ nrìn dede pẹlu, iwọ si npa ofin mọ́. 25 Ṣugbọn niti awọn Keferi ti o gbagbọ́, awa ti kọwe, a si ti pinnu rẹ̀ pe, ki nwọn pa ara wọn mọ kuro ninu ohun ti a fi rubọ si oriṣa, ati ẹ̀jẹ ati ohun ilọlọrùnpa, ati àgbere. 26 Nigbana ni Paulu mu awọn ọkunrin na; ni ijọ keji o ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn, o si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o sọ ìgba ti ọjọ ìwẹ̀numọ́ na yio pé titi a fi rubọ fun olukuluku wọn.

Wọ́n Mú Paulu ninu Tẹmpili

27 Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u. 28 Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ. 29 Nitori nwọn ti ri Trofimu ará Efesu pẹlu rẹ̀ ni ilu, ẹniti nwọn ṣebi Paulu mu wá sinu tẹmpili. 30 Gbogbo ilu si rọ́, awọn enia si sure jọ: nwọn si mu Paulu, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu tẹmpili: lojukanna a si tì ilẹkun. 31 Bi nwọn si ti nwá ọ̀na ati pa a, ìhin de ọdọ olori ẹgbẹ ọmọ-ogun pe, gbogbo Jerusalemu dàrú. 32 Lojukanna o si ti mu awọn ọmọ-ogun ati awọn balogun ọrún, o si sure sọkalẹ tọ̀ wọn lọ: nigbati nwọn si ri olori ogun ati awọn ọmọ-ogun, nwọn dẹkun lilu Paulu. 33 Nigbana li olori ogun sunmọ wọn, o si mu u, o paṣẹ pe ki a fi ẹ̀wọn meji dè e; o si bère ẹniti iṣe, ati ohun ti o ṣe. 34 Awọn kan nkígbe ohun kan, awọn miran nkigbe ohun miran ninu awujọ: nigbati kò si le mọ̀ eredi irukerudò na dajudaju, o paṣẹ ki nwọn ki o mu u lọ sinu ile-olodi. 35 Nigbati o si de ori atẹgùn, gbigbé li a gbé e soke lọwọ awọn ọmọ-ogun nitori iwa-ipa awọn enia. 36 Nitori ọ̀pọ enia gbátì i, nwọn nkigbe pe, Mu u kuro.

Paulu Rojọ́

37 Bi nwọn si ti fẹrẹ imu Paulu wọ̀ inu ile-olodi lọ, o wi fun olori-ogun pe, Emi ha gbọdọ ba ọ sọ̀rọ? O si dahùn wipe, Iwọ mọ̀ ède Hellene ifọ̀? 38 Iwọ ha kọ́ ni ara Egipti nì, ti o ṣọ̀tẹ ṣaju ọjọ wọnyi, ti o si ti mu ẹgbaji ọkunrin ninu awọn ti iṣe apania lẹhin lọ si iju? 39 Ṣugbọn Paulu si wipe, Ju li emi iṣe, ara Tarsu ilu Kilikia, ọlọ̀tọ ilu ti kì iṣe ilu lasan kan, emi si bẹ ọ, bùn mi lãye lati ba awọn enia sọrọ. 40 Nigbati o si ti bùn u lãye, Paulu duro lori atẹgùn, o si juwọ́ si awọn enia. Nigbati nwọn si dakẹrọrọ o ba wọn sọrọ li ède Heberu, wipe,

Iṣe 22

1 ẸNYIN ará, ati baba, ẹ gbọ ti ẹnu mi nisisiyi. 2 (Nigbati nwọn si gbọ́ pe o mba wọn sọrọ li ede Heberu, nwọn tubọ parọrọ; o si wipe,) 3 Ju li emi iṣe ẹniti a bí ni Tarsu ilu kan ni Kilikia, ṣugbọn ti a tọ́ ni ilu yi, li ẹsẹ Gamalieli, ti a kọ́ gẹgẹ bi lile ofin awọn baba wa, ti mo si jẹ onitara fun Ọlọrun ani gẹgẹ bi gbogbo nyin ti ri li oni. 4 Mo si ṣe inunibini si Ọna yi titi o fi de iku, mo ndè, mo si nfi wọn sinu tubu, ati ọkunrin ati obinrin. 5 Bi olori alufa pẹlu ti jẹ mi li ẹri, ati gbogbo ajọ awọn alàgba: lọwọ awọn ẹniti mo si gbà iwe lọ sọdọ awọn arakunrin, ti mo si lọ si Damasku lati mu awọn ti o wà nibẹ̀ ni didè wá si Jerusalemu, lati jẹ wọn niyà.

Paulu Sọ Bí Ó Ṣe Di Onigbagbọ

6 O si ṣe, bi emi ti nlọ, ti mo si sunmọ eti Damasku niwọn ọjọkanri, li ojijì, imọlẹ nla mọ́ ti ọrun wá yi mi ká. 7 Mo si ṣubu lùlẹ, mo si ngbọ́ ohùn kan ti o wi fun mi pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? 8 Emi si dahùn wipe, Iwọ tani, Oluwa? O si wi fun mi pe, Emi Jesu ti Nasareti ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si. 9 Awọn ti o si wà pẹlu mi ri imọlẹ na nitõtọ, ẹ̀ru si ba wọn; ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ohùn ẹniti mba mi sọrọ. 10 Mo si wipe, Kini ki emi ki o ṣe, Oluwa? Oluwa si wi fun mi pe, Dide, ki o si lọ si Damasku; nibẹ̀ li a o si sọ ohun gbogbo fun ọ ti a yàn fun ọ lati ṣe. 11 Bi emi kò si ti le riran nitori itànṣan imọlẹ na, a ti ọwọ́ awọn ti o wà lọdọ mi fà mi, mo si de Damasku. 12 Ẹnikan si tọ̀ mi wá, Anania, ọkunrin olufọkansìn gẹgẹ bi ofin, ti o li orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Ju ti o ngbe ibẹ̀. 13 O si duro tì mi, o si wi fun mi pe, Saulu arakunrin, riran. Ni wakati kanna mo si ṣiju soke wò o. 14 O si wipe, Ọlọrun awọn baba wa yàn ọ, lati mọ̀ ifẹ rẹ̀, ati lati ri Olõtọ nì, ati lati gbọ́ ohùn li ẹnu rẹ̀, 15 Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹri rẹ̀ fun gbogbo enia, li ohun ti iwọ ti ri ti iwọ si ti gbọ́. 16 Njẹ nisisiyi kini iwọ nduro de? Dide, ki a si baptisi rẹ, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ nù, ki o si mã pè orukọ Oluwa.

A rán Paulu sí Àwọn tí Kì í Ṣe Juu

17 O si ṣe pe, nigbati mo pada wá si Jerusalemu, ti mo ngbadura ni tẹmpili mo bọ si ojuran; 18 Mo si ri i, o wi fun mi pe, Yara, ki o si jade kuro ni Jerusalemu kánkán: nitori nwọn kì yio gbà ẹrí rẹ nipa mi. 19 Emi si wipe, Oluwa, awọn pãpã mọ̀ pe, emi a ti mã sọ awọn ti o gbà ọ gbọ sinu tubu, emi a si mã lù wọn ninu sinagogu gbogbo: 20 Nigbati a si ta ẹ̀jẹ Stefanu ẹlẹri rẹ silẹ, emi na pẹlu duro nibẹ̀, mo si li ohùn si ikú rẹ̀, mo si nṣe itọju aṣọ awọn ẹniti o pa a. 21 O si wi fun mi pe, Mã lọ: nitori emi ó rán ọ si awọn Keferi lokere réré.

Paulu ati Ọ̀gágun Ọmọ Ìbílẹ̀ Romu

22 Nwọn si fi etí si i titi de ọ̀rọ yi, nwọn si gbé ohùn wọn soke wipe, Ẹ mu irú eyiyi kuro li aiye: nitori kò yẹ ki o wà lãye. 23 Bi nwọn si ti nkigbe, ti nwọn si wọ́n aṣọ wọn silẹ, ti nwọn nku ekuru si oju ọrun, 24 Olori ogun paṣẹ pe ki a mu u wá sinu ile-olodi, o ni ki a fi ẹgba bi i lẽre; ki on ki o le mọ̀ itori ohun ti nwọn ṣe nkigbe le e bẹ̃. 25 Bi nwọn si ti fi ọsán dè e, Paulu bi balogun ọrún ti o duro tì i pe, O ha tọ́ fun nyin lati nà ẹniti iṣe ará Romu li aijẹbi? 26 Nigbati balogun ọrún si gbọ́, o lọ, o wi fun olori-ogun pe, Kili o fẹ ṣe yi: nitori ọkunrin yi ara Romu ni iṣe. 27 Olori-ogun si de, o si bi i pe, Sọ fun mi, ara Romu ni iwọ iṣe? O si wipe, Bẹ̃ni. 28 Olori-ogun si dahùn wipe, Owo pupọ ni mo fi rà ọlá ibilẹ yi. Paulu si wipe, Ṣugbọn a bí emi bẹ̃ ni. 29 Nitorina awọn ti o mura lati bi i lẽre kuro lọdọ rẹ̀: lojukanna olori-ogun pẹlu si bẹ̀ru, nigbati o mọ̀ pe ara Romu ni iṣe, ati nitori o ti dè e.

Paulu Lọ Siwaju Àwọn Ìgbìmọ̀ Juu

30 Ni ijọ keji, nitoriti o fẹ mọ̀ dajudaju ohun ti awọn Ju nfi i sùn si, o tú u silẹ, o paṣẹ ki awọn olori alufa ati gbogbo igbimọ pejọ, o si mu Paulu sọkalẹ, o si mu u duro niwaju wọn.

Iṣe 23

1 NIGBATI Paulu si tẹjumọ igbimọ, o ni, Ará, emi ti nfi gbogbo ẹri-ọkàn rere lò aiye mi niwaju Ọlọrun titi fi di oni yi. 2 Anania olori alufa si paṣẹ fun awọn ti o duro tì i pe, ki o gbún u li ẹnu. 3 Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin? 4 Awọn ti o duro tì i si wipe, Olori alufa Ọlọrun ni iwọ ngàn? 5 Paulu si wipe, Ará, emi kò mọ̀ pe olori alufa ni: nitori a ti kọ ọ pe, Iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ olori awọn enia rẹ ni buburu. 6 Ṣugbọn nigbati Paulu ṣakiyesi pe, apakan wọn jẹ Sadusi, apakan si jẹ Farisi, o kigbe ni igbimọ pe, Ará, Farisi li emi, ọmọ Farisi: nitori ireti ati ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ. 7 Nigbati o si ti wi eyi, iyapa de lãrin awọn Farisi ati awọn Sadusi: ajọ si pin meji. 8 Nitoriti awọn Sadusi wipe, kò si ajinde, tabi angẹli, tabi ẹmí: ṣugbọn awọn Farisi jẹwọ mejeji. 9 O si di ariwo nla: ninu awọn akọwe ti o wà li apa ti awọn Farisi dide, nwọn njà, wipe, Awa kò ri ohun buburu kan lara ọkunrin yi: ki si ni bi ẹmi kan tabi angẹli kan li o ba a sọ̀rọ? 10 Nigbati iyapa si di nla, ti olori ogun bẹ̀ru ki Paulu ki o má bà di fifaya lọwọ wọn, o paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ogun sọkalẹ lọ lati fi ipá mu u kuro lãrin wọn, ki nwọn si mu u wá sinu ile-olodi. 11 Li oru ijọ na Oluwa duro tì i, o si wipe, Tujuka: nitori bi iwọ ti jẹri fun mi ni Jerusalemu, bẹ̃ni iwọ kò le ṣaijẹrí ni Romu pẹlu.

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Paulu

12 Nigbati ilẹ mọ́, awọn Ju kan dimọlu, nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ bẹ̃li awọn kì yio mu, titi awọn ó fi pa Paulu. 13 Awọn ti o ditẹ yi si jù ogoji enia lọ. 14 Nwọn si tọ̀ olori awọn alufa ati awọn àgbagba lọ, nwọn si wipe, Awa ti fi èpe nla bu ara wa pe, a kì yio tọ́ ohun nkan wò titi awa ó fi pa Paulu. 15 Njẹ nisisiyi ki ẹnyin pẹlu ajọ igbimọ wi fun olori-ogun, ki o mu u sọkalẹ tọ̀ nyin wá, bi ẹnipe ẹnyin nfẹ wadi ọ̀ran rẹ̀ dajudaju: ki o to sunmọ itosi, awa ó si ti mura lati pa a. 16 Nigbati ọmọ arabinrin Paulu si gburó idena wọn, o lọ, o si wọ̀ inu ile-olodi lọ, o si sọ fun Paulu. 17 Paulu si pè ọkan ninu awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o ni, Mu ọmọkunrin yi tọ̀ olori-ogun lọ: nitori o ni nkan lati sọ fun u. 18 O mu u, o si sìn i lọ sọdọ olori-ogun, o si wipe, Paulu ondè pè mi sọdọ rẹ̀, o si bẹ̀ mi pe ki emi mu ọmọkunrin yi tọ̀ ọ wá, ẹniti o ni nkan lati sọ fun ọ. 19 Olori-ogun fà a lọwọ, o si lọ si apakan, o si bi i lere nikọkọ pe, Kili ohun ti iwọ ni isọ fun mi? 20 O si wipe, Awọn Ju fi ìmọ ṣọkan lati wá ibẹ̀ ọ ki o mu Paulu sọkalẹ wá si ajọ igbimọ li ọla, bi ẹnipe iwọ nfẹ bère nkan dajudaju nipa rẹ̀. 21 Nitorina máṣe gbọ́ tiwọn: nitori awọn ti o dèna dè e ninu wọn jù ogoji ọkunrin lọ, ti nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ, bẹ̃li awọn kì yio mu titi awọn o fi pa a: nisisiyi nwọn si ti mura tan, nwọn nreti idahùn lọdọ rẹ. 22 Nigbana li olori ogun jọwọ ọmọkunrin na lọwọ lọ, o si kìlọ fun u pe, Máṣe wi fun ẹnikan pe, iwọ fi nkan wọnyi hàn mi.

A fi Paulu Ranṣẹ sí Fẹliksi Gomina

23 O si pè meji awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ mura igba ọmọ-ogun silẹ, lati lọ si Kesarea, ati adọrin ẹlẹṣin, ati igba ọlọkọ̀, ni wakati kẹta oru; 24 O si wipe, ki nwọn pèse ẹranko, ki nwọn gbé Paulu gùn u, ki nwọn si le mu u de ọdọ Feliksi bãlẹ li alafia. 25 O si kọ iwe kan bayi pe: 26 Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia. 27 Awọn Ju mu ọkunrin yi, nwọn si npete ati pa a: nigbana ni mo de pẹlu ogun, mo si gbà a lọwọ wọn nigbati mo gbọ́ pe ara Romu ni iṣe. 28 Nigbati mo si nfẹ mọ̀ idi ọ̀ran ti nwọn fi i sùn si, mo mu u sọkalẹ lọ si ajọ igbimọ wọn: 29 Ẹniti mo ri pe, nwọn fisùn nitori ọ̀ran ofin wọn, bẹ̃ni kò dà ọ̀ran kan ti o tọ́ si ikú ati si ìde. 30 Nigbati a si ti sọ fun mi pe, nwọn ó dèna dè ọkunrin na, ọgan mo si rán a si ọ, mo si paṣẹ fun awọn olufisùn rẹ̀ pẹlu, lati sọ ohun ti nwọn ba ri wi si i niwaju rẹ. 31 Nigbana li awọn ọmọ-ogun gbà Paulu, nwọn si mu u li oru lọ si Antipatri, gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun wọn. 32 Nijọ keji nwọn si jọwọ awọn ẹlẹṣin lati mã ba a lọ, nwọn si pada wá sinu ile-olodi. 33 Nigbati nwọn de Kesarea, ti nwọn si fi iwe fun bãlẹ, nwọn mu Paulu pẹlu wá siwaju rẹ̀. 34 Nigbati o si ti kà iwe na, o bère pe ara ilẹ wo ni iṣe. Nigbati o si gbọ́ pe ara Kilikia ni; 35 O ni, Emi ó gbọ́ ẹjọ rẹ, nigbati awọn olufisùn rẹ pẹlu ba de. O si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa a mọ́ ni gbọ̀ngan idajọ Herodu.

Iṣe 24

Ẹ̀sùn Tí Wọ́n fi Kan Paulu

1 LẸHIN ijọ marun Anania olori alufa ni sọkalẹ lọ pẹlu awọn alàgba ati ẹnikan Tertulu agbẹjọrò ẹniti o fi Paulu sùn bãlẹ. 2 Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi. 3 Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ. 4 Ṣugbọn ki emi ki o má bà da ọ duro pẹ titi, mo bẹ̀ ọ ki o fi iyọnu rẹ gbọ́ ọ̀rọ diẹ li ẹnu wa. 5 Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene: 6 Ẹniti o gbidanwo lati bà tẹmpili jẹ: ti awa si mu, ti awa fẹ ba ṣe ẹjọ gẹgẹ bi ofin wa. 7 Ṣugbọn Lisia olori ogun de, o fi agbara nla gbà a li ọwọ wa: 8 O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀. 9 Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.

Paulu Sọ Tẹnu Rẹ̀ Níwájú Fẹliksi

10 Nigbati bãlẹ ṣapẹrẹ si i pe ki o sọ̀rọ, Paulu si dahùn wipe, Bi mo ti mọ̀ pe lati ọdún melo yi wá, ni iwọ ti ṣe onidajọ orilẹ-ede yi, tayọtayọ ni ng o fi wi ti ẹnu mi. 11 Ki o le yé ọ pe, ijejila pére yi ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ jọsìn. 12 Bẹ̃ni nwọn kò ri mi ni tẹmpili ki emi ki o ma ba ẹnikẹni jiyàn, bẹ̃li emi kò rú awọn enia soke, ibaṣe ninu sinagogu, tabi ni ilu: 13 Bẹ̃ni nwọn kò le ladi ohun ti nwọn fi mi sùn si nisisiyi. 14 Ṣugbọn eyi ni mo jẹwọ fun ọ, pe bi Ọna ti a npè ni adamọ̀, bẹ̃li emi nsìn Ọlọrun awọn baba wa, emi ngbà nkan gbogbo gbọ́ gẹgẹ bi ofin, ati ti a kọ sinu iwe awọn woli: 15 Mo si ni ireti sipa ti Ọlọrun, eyi ti awọn tikarawọn pẹlu jẹwọ, pe ajinde okú mbọ̀, ati ti olõtọ, ati ti alaiṣõtọ. 16 Ninu eyi li emi si nṣe idaraya, lati ni ẹri-ọkàn ti kò li ẹ̀ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo. 17 Ṣugbọn lẹhin ọdún pipọ, mo mu ọrẹ-ãnu fun orilẹ-ède mi wá, ati ọrẹ-ẹbọ. 18 Larin wọnyi ni nwọn ri mi ni iwẹnu ni tẹmpili, bẹ̃ni kì iṣe pẹlu awujọ, tabi pẹlu ariwo. 19 Ṣugbọn awọn Ju lati Asia wà nibẹ, awọn ti iba wà nihinyi niwaju rẹ, ki nwọn ki o já mi ni koro, bi nwọn ba li ohunkohun si mi. 20 Bi kò ṣe bẹ̃, jẹ ki awọn enia wọnyi tikarawọn sọ iṣe buburu ti nwọn ri lọwọ mi, nigbati mo duro niwaju ajọ igbimọ yi, 21 Bikoṣe ti gbolohùn kan yi, ti mo ke nigbati mo duro li ãrin wọn, Nitori ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ lọdọ nyin loni yi. 22 Nigbati Feliksi gbọ́ nkan wọnyi, oye sa ye e li ayetan nipa Ọna na; o tú wọn ká na, o ni, Nigbati Lisia olori ogun ba sọkalẹ wá, emi o wadi ọ̀ran nyin daju. 23 O si paṣẹ fun balogun ọrún kan pe, ki o mã ṣe itọju Paulu, ki o si bùn u làye, ati pe ki o máṣe dá awọn ojulumọ̀ rẹ̀ lẹkun, lati ma ṣe iranṣẹ fun u.

Wọ́n Ti Paulu Mọ́lé

24 Ṣugbọn lẹhin ijọ melokan, Feliksi de ti on ti Drusilla obinrin rẹ̀, ti iṣe Ju, o si ranṣẹ pè Paulu, o si gbọ́ ọ̀rọ lọdọ rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. 25 Bi o si ti nsọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ̀, ẹ̀ru ba Feliksi, o dahùn wipe, Mã lọ nisisiyi na; nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ̀, emi o ranṣẹ pè ọ. 26 O si nreti pẹlu pe a ba fun on li owo lati ọwọ́ Paulu wá, ki on ki o le da a silẹ: nitorina a si ma ranṣẹ si i nigbakugba, a ma ba a sọ̀rọ. 27 Ṣugbọn lẹhin ọdún meji, Porkiu Festu rọpò Feliksi: Feliksi si nfẹ ṣe oju're fun awọn Ju, o fi Paulu silẹ li ondè.

Iṣe 25

Paulu Gbé Ẹjọ́ Rẹ̀ Lọ siwaju Ọba Kesari

1 NJẸ nigbati Festu de ilẹ na, lẹhin ijọ mẹta o gòke lati Kesarea lọ si Jerusalemu. 2 Awọn olori alufa ati awọn enia pataki ninu awọn Ju fi Paulu sùn u, nwọn si bẹ̀ ẹ, 3 Nwọn nwá oju're rẹ̀ si Paulu, ki o le ranṣẹ si i wá si Jerusalemu: nwọn ndèna dè e lati pa a li ọna. 4 Ṣugbọn Festu dahun pe, a pa Paulu mọ́ ni Kesarea, ati pe on tikara on nmura ati pada lọ ni lọ̃lọ̃yi. 5 O ni, njẹ awọn ti o ba to ninu nyin, ki nwọn ba mi sọkalẹ lọ, bi ìwa buburu kan ba wà lọwọ ọkunrin yi, ki nwọn ki o fi i sùn. 6 Kò si gbe ãrin wọn ju ijọ mẹjọ tabi mẹwa lọ, o sọkalẹ lọ si Kesarea; ni ijọ keji o joko lori itẹ́ idajọ, o si paṣẹ pè ki a mu Paulu wá. 7 Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi. 8 Paulu si wi ti ẹnu rẹ̀ pe, Emi kò ṣẹ ẹṣẹkẹṣẹ kan si ofin awọn Ju, tabi si tẹmpili, tabi si Kesari. 9 Ṣugbọn Festu nfẹ gbà oju're lọdọ awọn Ju, o si da Paulu lohùn, wipe, Iwọ ha nfẹ goke lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀ niwaju mi bi? 10 Paulu si wipe, Niwaju itẹ́ idajọ Kesari ni mo duro nibiti o yẹ ki a ṣe ẹjọ mi: emi kò ṣẹ awọn Ju, bi iwọ pẹlu ti mọ̀ daju. 11 Njẹ bi mo ba ṣẹ̀, ti mo si ṣe ohun kan ti o yẹ fùn ikú, emi kò kọ̀ lati kú: ṣugbọn bi kò ba si nkan wọnni ninu ohun ti awọn wọnyi fi mi sùn si, ẹnikan kò le fi mi ṣe oju're fun wọn. Mo fi ọ̀ran mi lọ Kesari. 12 Nigbana ni Festu lẹhin ti o ti ba ajọ igbìmọ sọ̀rọ, o dahùn pe, Iwọ ti fi ọ̀ran rẹ lọ Kesari: lọdọ Kesari ni iwọ ó lọ.

A Mú Paulu lọ Siwaju Agripa ati Bernike

13 Lẹhin ijọ melokan, Agrippa ọba, ati Bernike sọkalẹ wá si Kesarea lati kí Festu. 14 Bi nwọn si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, Festu mu ọ̀ran Paulu wá siwaju ọba, wipe, Feliksi fi ọkunrin kan silẹ li ondè: 15 Ẹniti awọn olori alufa ati awọn agbàgba awọn Ju fi sùn nigbati mo wà ni Jerusalemu nwọn nfẹ ki n da a lẹbi. 16 Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn, 17 Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá. 18 Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn. 19 Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye. 20 Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀. 21 Ṣugbọn nigbati Paulu fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, pe ki a pa on mọ fun idajọ rẹ̀, mo paṣẹ pe ki a pa a mọ titi emi o fi le rán a lọ sọdọ Kesari. 22 Agrippa si wi fun Festu pe, Emi pẹlu fẹ lati gbọ́ ọrọ ọkunrin na tikarami. O si wipe, Lọla iwọ o gbọ ọ. 23 Njẹ ni ijọ keji, ti Agrippa on Bernike wá, ti awọn ti ọsọ́ pipọ, ti nwọn si wọ ile ẹjọ, pẹlu awọn olori ogun, ati awọn enia nla ni ilu, Festu paṣẹ, nwọn si mu Paulu jade. 24 Festu si wipe, Agrippa ọba, ati gbogbo ẹnyin enia ti o wà nihin pẹlu wa, ẹnyin ri ọkunrin yi, nitori ẹniti gbogbo ijọ awọn Ju ti rọgbaká mi, ni Jerusalemu ati nihinyi, ti nwọn nkigbe pe, Kò yẹ fun u lati wà lãye mọ́. 25 Ṣugbọn emi ri pe, kò ṣe ohun kan ti o yẹ si ikú, bi on tikararẹ̀ si ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, mo ti pinnu lati rán a lọ. 26 Nipasẹ ẹniti emi kò ri ohun kan dajudaju lati kọwe si oluwa mi. Nitorina ni mo ṣe mu u jade wá siwaju nyin, ati pe siwaju rẹ, Agrippa ọba, pãpã lẹhin ti a ba ti wadi rẹ̀, ki emi ki o le ri ohun ti emi ó kọ. 27 Nitoriti kò tọ́ li oju mi lati rán ondè, ki a má si sọ ọ̀ran ti a kà si i lọrùn.

Iṣe 26

Paulu Sọ Ti Ẹnu Rẹ̀ níwájú Agiripa

1 AGRIPPA si wi fun Paulu pe, A fun ọ làye lati sọ ti ẹnu rẹ. Nigbana ni Paulu nawọ́, o si sọ ti ẹnu rẹ̀ pe: 2 Agrippa ọba, inu emi tikarami dùn nitoriti emi o wi ti ẹnu mi loni niwaju rẹ, niti gbogbo nkan ti awọn Ju nfi mi sùn si. 3 Pãpã bi iwọ ti mọ̀ gbogbo iṣe ati ọ̀ran ti mbẹ lãrin awọn Ju dajudaju, nitorina emi bẹ̀ ọ ki iwọ ki o fi sũru gbọ temi. 4 Iwà aiye mi lati igba ewe mi, bi o ti ri lati ibẹrẹ, lãrin orilẹ-ede mi ati ni Jerusalemu, ni gbogbo awọn Ju mọ̀. 5 Nitori nwọn mọ̀ mi lati ipilẹṣẹ, bi nwọn ba fẹ́ jẹri pe, gẹgẹ bi ẹya ìsin wa ti o le julọ, Farisi li emi. 6 Ati nisisiyi nitori ireti ileri ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn baba wa ni mo ṣe duro nihin fun idajọ. 7 Ileri eyiti awọn ẹ̀ya wa mejejila ti nfi itara sin Ọlọrun lọsan ati loru ti nwọn nreti ati ri gba. Nitori ireti yi li awọn Ju ṣe nfi mi sùn, Agrippa Ọba. 8 Ẽṣe ti ẹnyin fi rò o si ohun ti a kò le gbagbọ́ bi Ọlọrun ba jí okú dide? 9 Emi tilẹ rò ninu ara mi nitõtọ pe, o yẹ ki emi ki o ṣe ọpọlọpọ ohun òdi si orukọ Jesu ti Nasareti. 10 Eyi ni mo si ṣe ni Jerusalemu: awọn pipọ ninu awọn enia mimọ́ ni mo há mọ́ inu tubu, nigbati mo ti gbà aṣẹ lọdọ awọn olori alufa; nigbati nwọn si npa wọn, mo li ohùn si i. 11 Nigbapipọ ni mo ṣẹ́ wọn niṣẹ ninu gbogbo sinagogu, mo ndù u lati mu wọn sọ ọrọ-odi; nigbati mo ṣoro si wọn gidigidi, mo ṣe inunibini si wọn de àjeji ilu.

Paulu Sọ Bí Ó Ti Ṣe Di Onigbagbọ

12 Ninu rẹ̀ na bi mo ti nlọ si Damasku ti emi ti ọlá ati aṣẹ ikọ̀ lati ọdọ awọn olori alufa lọ, 13 Li ọsangangan, Ọba, mo ri imọlẹ kan lati ọrun wá, o jù riràn õrùn lọ, o mọlẹ yi mi ká, ati awọn ti o mba mi rè ajo. 14 Nigbati gbogbo wa si ṣubu lulẹ, mo gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si mi ni ède Heberu pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? Ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. 15 Emi si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi ni Jesu ti iwọ nṣe inunibini si. 16 Ṣugbọn dide, ki o si fi ẹsẹ rẹ tẹlẹ: nitori eyi ni mo ṣe farahàn ọ lati yàn ọ ni iranṣẹ ati ẹlẹri, fun ohun wọnni ti iwọ ti ri, ati ohun wọnni ti emi ó fi ara hàn fun ọ; 17 Emi o ma gbà ọ lọwọ awọn enia, ati lọwọ awọn Keferi, ti emi rán ọ si nisisiyi, 18 Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.

Ẹ̀rí tí Paulu Jẹ́ fún Àwọn Juu ati fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yòókù

19 Nitorina, Agrippa ọba, emi kò ṣe aigbọran si iran ọ̀run na. 20 Ṣugbọn mo kọ́ sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalemu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada. 21 Nitori nkan wọnyi li awọn Ju ṣe mu mi ni tẹmpili, ti nwọn si fẹ pa mi. 22 Ṣugbọn bi mo si ti ri iranlọwọ gbà lọdọ Ọlọrun, mo duro titi o fi di oni, mo njẹri fun ati ewe ati àgba, emi kò sọ ohun miran bikoṣe ohun ti awọn woli ati Mose ti wipe yio ṣẹ: 23 Pe, Kristi yio jìya, ati pe nipa ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, on ni yio kọ́ kede imọlẹ fun awọn enia ati fun awọn Keferi.

Paulu Fi Ẹ̀sìn Igbagbọ Lọ Agiripa

24 Bi o si ti nsọ t'ẹnu rẹ̀, Festu wi li ohùn rara pe, Paulu, ori rẹ bajẹ; ẹkọ́ akọjù ba ọ li ori jẹ. 25 Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade. 26 Nitori ọba mọ̀ nkan gbogbo wọnyi, niwaju ẹniti emi nsọ̀rọ li aibẹ̀ru: nitori mo gbagbọ pe ọkan ninu nkan wọnyi kò pamọ fun u, nitoriti a kò ṣe nkan yi ni ìkọkọ. 27 Agrippa ọba, iwọ gbà awọn woli gbọ́? Emi mọ̀ pe, iwọ gbagbọ́. 28 Agrippa si wi fun Paulu pe, Pẹlu ọrọ iyanju diẹ si i, iwọ iba sọ mi di Kristiani. 29 Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi. 30 Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko: 31 Nigbati nwọn lọ si apakan, nwọn ba ara wọn sọ pe, ọkunrin yi kò ṣe nkankan ti o yẹ si ikú tabi si ẹ̀wọn. 32 Agrippa si wi fun Festu pe, A ba dá ọkunrin yi silẹ ibamaṣepe kò ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Kesari.

Iṣe 27

Paulu Wọkọ̀ Lọ sí Romu

1 Bi a si ti pinnu rẹ̀ pe ki a wọ̀ ọkọ lọ si Itali, nwọn fi Paulu, ati awọn ondè miran kan pẹlu, le balogun ọrún kan lọwọ, ti a npè ni Juliu, ti ẹgbẹ ọmọ-ogun Augustu. 2 Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa. 3 Ni ijọ keji awa de Sidoni. Juliu si ṣe inu rere si Paulu, o si bùn u láye ki o mã tọ̀ awọn ọrẹ́ rẹ̀ lọ lati ri itọju. 4 Nigbati awa si ṣikọ̀ nibẹ̀, awa lọ lẹba Kipru, nitoriti afẹfẹ ṣọwọ òdi. 5 Nigbati awa ré okun Kilikia on Pamfilia kọja, awa de Mira Likia. 6 Nibẹ̀ ni balogun ọrún si ri ọkọ̀ Aleksandria kan, ti nlọ si Itali; o si fi wa sinu rẹ̀. 7 Nigbati awa nlọ jẹ́jẹ li ọjọ pipọ, ti awa fi agbara kaka de ọkankan Knidu, ti afẹfẹ kò bùn wa làye, awa lọ lẹba Krete, li ọkankan Salmone; 8 Nigbati a si fi agbara kaka kọja rẹ̀, awa de ibi ti a npè ni Ebute Yiyanjú, ti o sunmọ ibiti ilu Lasea ti wà ri. 9 Nigbati a si ti sọ ọjọ pipọ nù, ti a-ti ta igbokun wa idi ewu tan, nitori Awẹ ti kọja tan, Paulu da imọran, 10 O si wi fun wọn pe, Alàgba, mo woye pe iṣikọ̀ yi yio li ewu ati òfo pipọ, kì iṣe kìki ti ẹrù ati ti ọkọ̀, ṣugbọn ti ẹmí wa pẹlu. 11 Ṣugbọn balogun ọrún gbà ti olori ọkọ̀ ati ti ọlọkọ̀ gbọ́, jù ohun wọnni ti Paulu wi lọ. 12 Ati nitori ebute na kò rọrùn lati lo akoko otutu nibẹ̀, awọn pipọ si damọran pe, ki a lọ kuro nibẹ̀, bi nwọn ó le làkàka de Fenike lati lo akoko otutu, ti iṣe ebute Krete ti o kọju si òsi ìwọ õrùn, ati ọtún ìwọ õrùn.

Ìjì Jà ní Òkun

13 Nigbati afẹfẹ gusù si nfẹ jẹ́jẹ, ti nwọn ṣebi ọwọ awọn tẹ̀ ohun ti nwọn nwá, nwọn ṣikọ̀, nwọn npá ẹba Krete lọ. 14 Kò si pẹ lẹhin na ni ìji ti a npè ni Eurakuilo fẹ lù u. 15 Nigbati o si ti gbé ọkọ̀, ti kò si le dojukọ ìji na, awa jọwọ rẹ̀, o ngbá a lọ. 16 Nigbati o si gbá a lọ labẹ erekuṣu kan ti a npè ni Klauda, o di iṣẹ pipọ ki awa ki o to le sunmọ igbaja. 17 Nigbati nwọn si gbé e soke, nwọn nṣe iranlọwọ, nwọn ndì ọkọ ni isalẹ; nigbati nwọn si bẹ̀ru ki a ma ba gbá wọn sori iyanrìn diẹ̀, nwọn tagbokun, nwọn si ngbá kiri. 18 Bi awa si ti nṣe lãlã gidigidi ninu ìji na, ni ijọ keji nwọn kó nkan dà si omi lati mu ọkọ̀ fẹrẹ; 19 Ati ni ijọ kẹta, a fi ọwọ́ ara wa kó ohun èlo ọkọ̀ danu. 20 Nigbati õrùn ati irawọ kò si hàn li ọjọ pipọ, ti ìji na kò si mọ̀ niwọn fun wa, abá a-ti-là kò si fun wa mọ́. 21 Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa. 22 Njẹ nisisiyi mo gbà nyin niyanju, ki ẹ tújuka: nitori kì yio si òfo ẹmí ninu nyin, bikoṣe ti ọkọ̀. 23 Nitori angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi iṣe, ati ẹniti emi nsìn, o duro tì mi li oru aná, 24 O wipe, Má bẹ̀ru, Paulu; iwọ kò le ṣaima duro niwaju Kesari: si wo o, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ. 25 Njẹ nitorina, alàgba, ẹ daraya: nitori mo gbà Ọlọrun gbọ́ pe, yio ri bẹ̃ gẹgẹ bi a ti sọ fun mi. 26 Ṣugbọn a ó gbá wa jù si erekuṣu kan. 27 Ṣugbọn nigbati o di oru ijọ kẹrinla, ti awa ngbá sihin sọhún ni Adria, larin ọganjọ awọn atukọ̀ tànmã pe, awọn sunmọ eti ilẹ kan; 28 Nigbati nwọn si wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn li ogún àgbaká: nigbati nwọn si sún siwaju diẹ, nwọn si tún wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn ni àgbaká mẹ̃dogun. 29 Nigbati nwọn bẹ̀ru ki nwọn ki o máṣe gbá lù ibi okuta, nwọn sọ idakọró mẹrin silẹ ni idi ọkọ̀, nwọn nreti ojumọ́. 30 Ṣugbọn nigbati awọn atukọ̀ nwá ọ̀na ati sá kuro ninu ọkọ̀, ti nwọn si ti sọ igbaja kalẹ si oju okun bi ẹnipe nwọn nfẹ sọ idakọró silẹ niwaju ọkọ̀, 31 Paulu wi fun balogun ọrún ati fun awọn ọmọ-ogun pe, Bikoṣepe awọn wọnyi ba duro ninu ọkọ̀ ẹnyin kì yio le là. 32 Nigbana li awọn ọmọ-ogun ke okùn igbaja, nwọn jọwọ rẹ̀ ki o ṣubu sọhún. 33 Nigbati ilẹ nmọ́ bọ̀, Paulu bẹ̀ gbogbo wọn ki nwọn ki o jẹun diẹ, o wipe, Oni li o di ijẹrinla ti ẹnyin ti nreti, ti ẹ kò dẹkun gbãwẹ, ti ẹ kò si jẹun. 34 Nitorina mo bẹ̀ nyin, ki ẹ jẹun diẹ: nitori eyi ni fun igbala nyin: nitori irun kan kì yio re kuro li ori ẹnikan nyin. 35 Nigbati o si wi nkan wọnyi, ti o si mu akara, o dupẹ lọwọ Ọlọrun niwaju gbogbo wọn: nigbati o si bù u, o bẹ̀rẹ si ijẹ. 36 Nigbana ni gbogbo wọn si daraya, awọn pẹlu si gbà onjẹ. 37 Gbogbo wa ti mbẹ ninu ọkọ̀ na si jẹ ọrinlugba ọkàn o dí mẹrin. 38 Nigbati nwọn jẹun yó tan, nwọn kó nkan danù kuro ninu ọkọ̀, nwọn si kó alikama dà si omi.

Ọkọ̀ Rì

39 Nigbati ilẹ si mọ, nwọn kò mọ̀ ilẹ na: ṣugbọn nwọn ri apa odò kan ti o li ebute, nibẹ̀ ni nwọn gbero, bi nwọn o ba le tì ọkọ̀ si. 40 Nigbati nwọn si ké idakọró kuro, nwọn jọ̀wọ wọn sinu okun, lẹsẹkanna nwọn tu ide ọkọ̀, nwọn si ta igbokun iwaju ọkọ̀ si afẹfẹ, nwọn wa kọju si ilẹ. 41 Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na. 42 Ero awọn ọmọ-ogun ni ki a pa awọn onde, ki ẹnikẹni wọn ki o má ba wẹ̀ jade sá lọ. 43 Ṣugbọn balogun ọrún nfẹ gbà Paulu là, o kọ̀ ero wọn; o si paṣẹ fun awọn ti o le wẹ̀ ki nwọn ki o kọ́ bọ si okun lọ si ilẹ, 44 Ati awọn iyokù, omiran lori apako, ati omiran lori ẹfọkọ̀. Bẹ̃li o si ṣe ti gbogbo wọn yọ, li alafia de ilẹ.

Iṣe 28

Ohun tí Paulu Ṣe ní Erékùṣù Mẹlita

1 NIGBATI gbogbo wa si yọ tan ni awa mọ̀ pe, Melita li a npè erekuṣu na. 2 Kì si iṣe ore diẹ li awọn alaigbede na ṣe fun wa: nitoriti nwọn daná, nwọn si gbà gbogbo wa si ọdọ nitori òjo igba na, ati itori otutù. 3 Nigbati Paulu si ṣà ìdi iwọ́nwọ́n igi jọ, ti o si kó o sinu iná, pamọlẹ kan ti inu oru jade, o dì mọ́ ọ li ọwọ́. 4 Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye. 5 On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e. 6 Ṣugbọn nwọn nwoye igbati yio wú, tabi ti yio si ṣubu lulẹ kú lojiji: nigbati nwọn wò titi, ti nwọn kò si ri nkankan ki o ṣe e, nwọn pa iyè da pe, oriṣa kan li ọkunrin yi. 7 Li àgbegbe ibẹ̀ ni ilẹ ọkunrin ọlọlá erekuṣu na wà, orukọ ẹniti a npè ni Publiu; ẹniti o gbà wa si ọdọ, ti o si fi inu rere mu wa wọ̀ ni ijọ mẹta. 8 O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada. 9 Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada: 10 Awọn ẹniti o bù ọlá pipọ fun wa; nigbati awa si nlọ, nwọn dì nkan gbogbo rù wa ti a ba ṣe alaini.

Paulu Dé Romu

11 Ati lẹhin oṣù mẹta awa wọ̀ ọkọ Aleksandria kan, ti o lo akoko otutu li erekuṣu na, àmi eyi ti iṣe Kastoru on Poluksu. 12 Nigbati awa gúnlẹ ni Sirakuse, awa gbé ibẹ̀ ni ijọ mẹta. 13 Lati ibẹ̀ nigbati awa lọ yiká, awa de Regioni: ati lẹhin ijọ kan afẹfẹ gusù dide, ni ijọ keji rẹ̀ awa si de Puteoli, 14 Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu. 15 Ati lati ibẹ nigbati awọn arakunrin gburó wa, nwọn wá titi nwọn fi de Apii Foroni, ati Arojẹ mẹta, lati pade wa: nigbati Paulu si ri wọn, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, o mu ọkàn le.

Paulu Waasu ní Romu

16 Nigbati awa si de Romu, balogun ọrún fi awọn ondè le olori ẹṣọ́ lọwọ: ṣugbọn nwọn jẹ ki Paulu ki o mã dagbe fun ara rẹ̀ pẹlu ọmọ-ogun ti ṣọ́ ọ. 17 O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta, Paulu pè awọn olori Ju jọ: nigbati nwọn si pejọ, o wi fun wọn pe, Ará, biotiṣe pe emi kò ṣe ohun kan lòdi si awọn enia, tabi si iṣe awọn baba wa, sibẹ nwọn fi mi le awọn ara Romu lọwọ li ondè lati Jerusalemu wá. 18 Nigbati nwọn si wádi ọ̀ran mi, nwọn fẹ jọwọ mi lọwọ lọ, nitoriti kò si ọ̀ran ikú lara mi. 19 Ṣugbọn nigbati awọn Ju sọ̀rọ lòdi si i, eyi sún mi lati fi ọ̀ran mi lọ Kesari; kì iṣe pe mo ni nkan lati fi orilẹ-ède mi sùn si. 20 Njẹ nitori ọ̀ran yi ni mo ṣe ranṣẹ pè nyin, lati ri nyin, ati lati ba nyin sọ̀rọ: nitoripe nitori ireti Israeli li a ṣe fi ẹ̀wọn yi dè mi. 21 Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ri iwe gbà lati Judea wá nitori rẹ, bẹ̃li ẹnikan ninu awọn arakunrin ti o ti ibẹ̀ wá kò rohin, tabi ki o sọ̀rọ ibi kan si ọ. 22 Ṣugbọn awa nfẹ gbọ́ li ẹnu rẹ ohun ti iwọ rò: nitori bi o ṣe ti ìsin iyapa yi ni, awa mọ̀ pe, nibigbogbo li a nsọ̀rọ lòdi si i. 23 Nigbati nwọn dá ọjọ fun u, ọ̀pọlọpọ wọn li o tọ̀ ọ wá ni ile àgbawọ rẹ̀; awọn ẹniti o sọ asọye ọrọ ijọba Ọlọrun fun, o nyi wọn lọkàn pada sipa ti Jesu, lati inu ofin Mose ati awọn woli wá, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ. 24 Ẹlomiran si gbà ohun ti o nwi gbọ́, ẹlomiran kò si gbagbọ́. 25 Nigbati ohùn wọn kò ṣọ̀kan lãrin ara wọn, nwọn tuká, lẹhin igbati Paulu sọ̀rọ kan pe, Otitọ li Ẹmí Mimọ́ sọ lati ẹnu woli Isaiah wá fun awọn baba wa, 26 Wipe, Tọ̀ awọn enia wọnyi lọ, ki o si wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati ni riri ẹnyin ó ri, ẹnyin kì yio si woye: 27 Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo lati fi gbọ́, oju wọn ni nwọn si ti dì: nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ati ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ati ki emi ki o má ba mu wọn larada. 28 Njẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, a rán igbala Ọlọrun si awọn Keferi, nwọn ó si gbọ́. 29 Nigbati o si ti sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn tan, awọn Ju lọ, nwọn ba ara wọn jiyàn pipọ. 30 Paulu si gbe ile àgbawọ rẹ̀ lọdun meji tọ̀tọ, o si ngbà gbogbo awọn ti o wọle tọ̀ ọ wá, 31 O nwasu ijọba Ọlọrun, o si nfi igboiya gbogbo kọ́ni li ohun wọnni ti iṣe ti Jesu Kristi Oluwa, ẹnikan kò da a lẹkun.

Romu 1

Ìkíni

1 PAULU, iranṣẹ Jesu Kristi, ti a pè lati jẹ aposteli, ti a yà sọ̀tọ fun ihinrere Ọlọrun, 2 (Ti o ti ṣe ileri tẹlẹ rí ninu iwe-mimọ́, lati ọwọ awọn woli rẹ̀), 3 Niti Ọmọ rẹ̀, ti a bí lati inu irú-ọmọ Dafidi nipa ti ara, 4 Ẹniti a pinnu rẹ̀ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ẹmí iwa mimọ́, nipa ajinde kuro ninu okú, ani Jesu Kristi Oluwa wa: 5 Lati ọdọ ẹniti awa ri ore-ọfẹ ati iṣẹ aposteli gbà, fun igbọràn igbagbọ́ lãrin gbogbo orilẹ-ède, nitori orukọ rẹ̀: 6 Larin awọn ẹniti ẹnyin pẹlu ti a pè lati jẹ ti Jesu Kristi: 7 Si gbogbo ẹniti o wà ni Romu, olufẹ Ọlọrun, ti a pè lati jẹ mimọ́: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa wá, ati Jesu Kristi Oluwa.

Paulu Ṣàníyàn láti Lọ sí Romu

8 Mo kọ́ dupẹ na lọwọ Ọlọrun mi nipasẹ Jesu Kristi nitori gbogbo nyin, nitoripe a nròhin igbagbọ́ nyin yi gbogbo aiye ká. 9 Ọlọrun sá li ẹlẹri mi, ẹniti emi nfi ẹmi mi sìn ninu ihinrere Ọmọ rẹ̀, biotiṣepe li aisimi li emi nranti nyin nigbagbogbo ninu adura mi; 10 Emi mbẹ̀bẹ, bi lọna-kọna leke gbogbo rẹ̀, ki a le ṣe ọ̀na mi ni ire nipa ifẹ Ọlọrun, lati tọ̀ nyin wá. 11 Nitoriti emi nfẹ gidigidi lati ri nyin, ki emi ki o le fun nyin li ẹ̀bun ẹmi diẹ, ki a le fi ẹsẹ nyin mulẹ; 12 Eyini ni, ki a le jùmọ ni itunu ninu nyin nipa igbagbọ́ awa mejeji, ti nyin ati ti emi. 13 Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù. 14 Mo di ajigbese awọn Hellene ati awọn alaigbede; awọn ọlọ́gbọn ati awọn alaigbọn. 15 Tobẹ̃ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu.

Agbára Ìyìn Rere

16 Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu. 17 Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.

Gbogbo Aráyé Jẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀

18 Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀: 19 Nitori ohun ti ã le mọ̀ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn. 20 Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi: 21 Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun. 22 Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere, 23 Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò. 24 Nitorina li Ọlọrun ṣe fi wọn silẹ ninu ifẹkufẹ ọkàn wọn si ìwa-ẽri lati ṣe aibọ̀wọ fun ara wọn larin ara wọn: 25 Awọn ẹniti o yi otitọ Ọlọrun pada si eke, nwọn si bọ, nwọn si sìn ẹda jù Ẹlẹda lọ, ẹniti iṣe olubukun titi lai. Amin. 26 Nitori eyiyi li Ọlọrun ṣe fi wọn fun ifẹ iwakiwa: nitori awọn obinrin wọn tilẹ yi ilo ẹda pada si eyi ti o lodi si ẹda: 27 Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si. 28 Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́: 29 Nwọn kún fun aiṣododo gbogbo, àgbere, ìka, ojukòkoro, arankan; nwọn kún fun ilara, ipania, ija, itanjẹ, iwa-buburu; afi-ọrọ-kẹlẹ banijẹ, 30 Asọrọ ẹni lẹhin, akorira Ọlọrun, alafojudi, agberaga, ahalẹ, alaroṣe ohun buburu, aṣaigbọran si obí, 31 Alainiyè-ninu, ọ̀dalẹ, alainifẹ, agídi, alailãnu: 32 Awọn ẹniti o mọ̀ ilana Ọlọrun pe, ẹniti o ba ṣe irú nkan wọnyi, o yẹ si ikú, nwọn kò ṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn nwọn ni inu didùn si awọn ti nṣe wọn.

Romu 2

Ìdájọ́ Òdodo Tí Ọlọrun Ṣe

1 NITORINA alairiwi ni iwọ ọkunrin na, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ ti ndajọ: nitori ninu ohun ti iwọ nṣe idajọ ẹlomiran, iwọ ndá ara rẹ lẹbi; nitori iwọ ti ndajọ nṣe ohun kanna. 2 Ṣugbọn awa mọ̀ pe idajọ Ọlọrun jẹ gẹgẹ bi otitọ si gbogbo awọn ti o nṣe irú ohun bawọnni. 3 Ati iwọ ọkunrin na ti nṣe idajọ awọn ti nṣe irú ohun bawọnni, ti iwọ si nṣe bẹ̃ na, iwọ ro eyi pe iwọ ó yọ ninu idajọ Ọlọrun? 4 Tabi iwọ ngàn ọrọ̀ ore ati ipamọra ati sũru rẹ̀, li aimọ̀ pe ore Ọlọrun li o nfà ọ lọ si ironupiwada? 5 Ṣugbọn gẹgẹ bi lile ati aironupiwada ọkàn rẹ, ni iwọ nfi ibinu ṣura fun ara rẹ de ọjọ ibinu ati ti ifihàn idajọ ododo Ọlọrun: 6 Ẹniti yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: 7 Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun; 8 Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà. 9 Ipọnju ati irora, lori olukuluku ọkàn enia ti nhuwa ibi, ti Ju ṣaju, ati ti Hellene pẹlu; 10 Ṣugbọn ogo, ati ọlá, ati alafia, fun olukuluku ẹni ti nhuwa rere, fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu: 11 Nitori ojuṣaju enia kò si lọdọ Ọlọrun. 12 Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ; 13 Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare. 14 Nitori nigbati awọn Keferi, ti kò li ofin, ba ṣe ohun ti o wà ninu ofin nipa ẹda, awọn wọnyi ti kò li ofin, jẹ ofin fun ara wọn: 15 Awọn ẹniti o fihan pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn li ọkàn, ti ọkàn wọn si njẹ wọn lẹri, ti iro wọn larin ara wọn si nfi wọn sùn tabi ti o ngbè wọn, 16 Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi.

Àwọn Juu ati Òfin

17 Ṣugbọn bi a ba npè iwọ ni Ju, ti o si simi le ofin, ti o si nṣogo ninu Ọlọrun, 18 Ti o si mọ̀ ifẹ rẹ̀, ti o si dán ohun ti o yàtọ wò, ẹniti a ti kọ li ofin; 19 Ti o si gbé oju le ara rẹ̀ pe iwọ li amọ̀na awọn afọju, imọlẹ awọn ti o wà li òkunkun, 20 Olukọ awọn alaimoye, olukọ awọn ọmọde, ẹniti o ni afarawe imọ ati otitọ ofin li ọwọ. 21 Njẹ iwọ ti o nkọ́ ẹlomiran, iwọ kò kọ́ ara rẹ? iwọ ti o nwasu ki enia ki o má jale, iwọ njale? 22 Iwọ ti o nwipe ki enia ki o máṣe panṣaga, iwọ nṣe panṣaga? iwọ ti o ṣe họ̃ si oriṣa, iwọ njà tẹmpili li ole? 23 Iwọ ti nṣogo ninu ofin, ni riru ofin iwọ bù Ọlọrun li ọlá kù? 24 Nitori orukọ Ọlọrun sá di isọrọ-buburu si ninu awọn Keferi nitori nyin, gẹgẹ bi a ti kọ ọ. 25 Nitori ikọla li ère lõtọ, bi iwọ ba pa ofin mọ́: ṣugbọn bi iwọ ba jẹ arufin, ikọla rẹ di aikọla. 26 Nitorina bi alaikọla ba pa ilana ofin mọ́, a kì yio ha kà aikọla rẹ̀ si ikọla bi? 27 Alaikọla nipa ti ẹda, bi o ba pa ofin mọ́, kì yio ha da ẹbi fun iwọ ti o jẹ arufin nipa ti iwe ati ikọla? 28 Kì iṣe eyi ti o farahan ni Ju, bẹni kì iṣe eyi ti o farahan li ara ni ikọla: 29 Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.

Romu 3

1 NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ? 2 Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ. 3 Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi? 4 Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ. 5 Ṣugbọn bi aiṣododo wa ba nyìn ododo Ọlọrun, kili awa o wi? Ọlọrun ti nfi ibinu rẹ̀ han ha ṣe alaiṣododo bi? (Mo fi ṣe akawe bi enia.) 6 Ki a má ri: bi bẹ̃ni, Ọlọrun yio ha ṣe le dajọ araiye? 7 Nitori bi otitọ Ọlọrun ba di pipọ si iyìn rẹ̀ nitori eke mi, ẽṣe ti a fi nda mi lẹjọ bi ẹlẹṣẹ mọ́ si? 8 Ẽṣe ti a kò si wipe (gẹgẹ bi a ti nsọrọ wa ni ibi, ati gẹgẹ bi awọn kan ti nsọ pe, awa nwipe,) Ẹ jẹ ki a mã ṣe buburu, ki rere ki o le jade wá? awọn ẹniti ẹ̀bi wọn tọ́.

Kò Sí Olódodo Kan

9 Njẹ ki ha ni? awa ha san jù wọn bi? Kò ri bẹ̃ rara: nitori a ti fihan ṣaju pe ati awọn Ju ati awọn Hellene, gbogbo nwọn li o wà labẹ ẹ̀ṣẹ; 10 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: 11 Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. 12 Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan. 13 Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: 14 Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: 15 Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: 16 Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: 17 Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: 18 Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn. 19 Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun. 20 Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.

Ìdáláre Nípa Igbagbọ

21 Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli; 22 Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ: 23 Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; 24 Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: 25 Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun; 26 Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́. 27 Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́. 28 Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin. 29 Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu: 30 Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn. 31 Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ.

Romu 4

Àpẹẹrẹ Abrahamu

1 NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri? 2 Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun. 3 Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u. 4 Njẹ fun ẹniti o ṣiṣẹ a kò kà ère na si ore-ọfẹ bikoṣe si gbese. 5 Ṣugbọn fun ẹniti kò ṣiṣẹ, ti o si ngbà ẹniti o nda enia buburu lare gbọ́, a kà igbagbọ́ rẹ̀ si ododo. 6 Gẹgẹ bi Dafidi pẹlu ti pe oluwarẹ̀ na ni ẹni ibukun, ẹniti Ọlọrun kà ododo si laisi ti iṣẹ́, 7 Wipe, Ibukún ni fun awọn ẹniti a dari irekọja wọn jì, ti a si bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. 8 Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si li ọrùn. 9 Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo. 10 Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni. 11 O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu: 12 Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla.

Ìlérí Ṣẹ Nípa Igbagbọ

13 Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́. 14 Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara: 15 Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀. 16 Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa, 17 (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà; 18 Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri. 19 Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara: 20 Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; 21 Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e. 22 Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u. 23 A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u, 24 Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú; 25 Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.

Romu 5

Àyọrísí Ìdáláre

1 NJẸ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ́, awa ni alafia lọdọ Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi: 2 Nipasẹ ẹniti awa si ti ri ọ̀na gbà nipa igbagbọ́ si inu ore-ọfẹ yi ninu eyi ti awa gbé duro, awa si nyọ̀ ni ireti ogo Ọlọrun. 3 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa si nṣogo ninu wahalà pẹlu: bi a ti mọ̀ pe wahalà nṣiṣẹ sũru; 4 Ati sũru nṣiṣẹ iriri; ati iriri ni nṣiṣẹ ireti: 5 Ireti kì si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọ́kàn lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ wá ti a fifun wa. 6 Nitori igbati awa jẹ alailera, li akokò ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun. 7 Nitori o ṣọ̀wọn ki ẹnikan ki o to kú fun olododo: ṣugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le dába ati kú. 8 Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa. 9 Melomelo si ni, ti a da wa lare nisisiyi nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, li a o gbà wa là kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ̀. 10 Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀. 11 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa nṣogo ninu Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti awa ti ri ìlaja gbà nisisiyi.

Adamu ati Kristi

12 Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀: 13 Nitori ki ofin ki o to de, ẹ̀ṣẹ ti wà li aiye; ṣugbọn a kò kà ẹ̀ṣẹ si ni lọrun nigbati ofin kò si. 14 Ṣugbọn ikú jọba lati igbà Adamu wá titi fi di igba ti Mose, ati lori awọn ti kò ṣẹ̀ bi afarawe irekọja Adamu, ẹniti iṣe apẹrẹ ẹniti mbọ̀. 15 Ṣugbọn kì iṣe bi ẹ̀ṣẹ bẹ̃ si li ẹ̀bun ọfẹ. Nitori bi nipa ẹ̀ṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ kú, melomelo li ore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹ̀bun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ. 16 Kì isi ṣe bi nipa ẹnikan ti o ṣẹ̀, li ẹ̀bun na: nitori idajọ ti ipasẹ ẹnikan wá fun idalẹbi ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ ti inu ẹ̀ṣẹ pupọ wá fun idalare. 17 Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ ọkunrin kan ikú jọba nipasẹ ẹnikanna; melomelo li awọn ti ngbà ọ̀pọlọpọ ore-ọfẹ ati ẹ̀bun ododo yio jọba ninu ìye nipasẹ ẹnikan, Jesu Kristi. 18 Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ kan idajọ de bá gbogbo enia si idalẹbi; gẹgẹ bẹ̃ni nipa iwa ododo kan, ẹ̀bun ọfẹ de sori gbogbo enia fun idalare si ìye. 19 Nitori gẹgẹ bi nipa aigbọran enia kan, enia pupọ di ẹlẹṣẹ bẹ̃ ni nipa igbọran ẹnikan, a o sọ enia pupọ di olododo. 20 Ṣugbọn ofin bọ si inu rẹ̀, ki ẹ̀ṣẹ le di pupọ. Ṣugbọn nibiti ẹ̀ṣẹ di pupọ, ore-ọfẹ di pupọ rekọja, 21 Pe, gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti jọba nipa ikú, bẹni ki ore-ọfẹ si le jọba nipa ododo titi ìye ainipẹkun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.

Romu 6

Ikú sí Ẹ̀ṣẹ̀, Ìyè ninu Kristi

1 NJẸ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹ̀ṣẹ, ki ore-ọfẹ ki o le ma pọ̀ si i? 2 Ki a má ri. Awa ẹniti o ti kú si ẹ̀ṣẹ, awa o ha ṣe wà lãye ninu rẹ̀ mọ́? 3 Tabi ẹ kò mọ̀ pe, gbogbo wa ti a ti baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rẹ̀? 4 Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa. 5 Nitori bi a ba ti so wa pọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe ikú rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀: 6 Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́. 7 Nitori ẹniti o kú, o bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ. 8 Ṣugbọn bi awa ba bá Kristi kú, awa gbagbọ́ pe awa ó si wà lãye pẹlu rẹ̀: 9 Nitori awa mọ̀ pé bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú, kò ni ikú mọ́; ikú kò ni ipa lori rẹ̀ mọ́. 10 Nitori iku ti o kú, o kú si ẹ̀ṣẹ lẹ̃kan: nitori wiwà ti o wà lãye, o wà lãye si Ọlọrun. 11 Bẹ̃ni ki ẹnyin pẹlu kà ara nyin bi okú si ẹ̀ṣẹ, ṣugbọn bi alãye si Ọlọrun ninu Kristi Jesu. 12 Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀; 13 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun. 14 Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.

Ẹrú Òdodo

15 Njẹ kini? ki awa ki o ha ma dẹṣẹ̀, nitoriti awa kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ? Ki a má ri. 16 Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo? 17 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ. 18 Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo. 19 Emi nsọ̀rọ bi enia nitori ailera ara nyin: nitori bi ẹnyin ti jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ bi ẹrú fun iwa-ẽri ati fun ẹ̀ṣẹ de inu ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹnyin ki o jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ nisisiyi bi ẹrú fun ododo si ìwa-mimọ́. 20 Nitori nigbati ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ, ẹnyin wà li omnira si ododo. 21 Njẹ eso kili ẹnyin ha ni nigbana ninu ohun ti oju ntì nyin si nisisiyi? nitori opin nkan wọnni ikú ni. 22 Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun. 23 Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

Romu 7

Àpẹẹrẹ Láti Inú Igbeyawo

1 TABI ẹnyin ha ṣe alaimọ̀, ará (nitori awọn ti o mọ̀ ofin li emi mba sọrọ), pe ofin ni ipa lori enia niwọn igbati o ba wà lãye? 2 Nitori obinrin ti o ni ọkọ, ìwọn igbati ọkọ na wà lãye, a fi ofin dè e mọ́ ọkọ na; ṣugbọn bi ọkọ na ba kú, a tú u silẹ kuro ninu ofin ọkọ na. 3 Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rẹ̀ wà lãye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran. 4 Bẹ̃li ẹnyin ará mi, ẹnyin pẹlu ti di okú si ofin nipa ara Kristi: ki ẹnyin kì o le ni ẹlomiran, ani ẹniti a jinde kuro ninu okú, ki awa ki o le so eso fun Ọlọrun. 5 Nitori igbati awa wà nipa ti ara, ifẹkufẹ ẹ̀ṣẹ, ti o wà nipa ofin, o nṣiṣẹ ninu awọn ẹ̀ya ara wa lati so eso si ikú. 6 Ṣugbọn nisisiyi a fi wa silẹ kuro ninu ofin, nitori a ti kú si eyiti a ti dè wa sinu rẹ̀: ki awa ki o le mã sìn li ọtun Ẹmí, ki o má ṣe ni ode ara ti atijọ.

Bí Òfin Ti ń Mú Eniyan Dẹ́ṣẹ̀

7 Njẹ awa o ha ti wi? ofin ha iṣe ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri. Ṣugbọn emi kò ti mọ̀ ẹ̀ṣẹ, bikoṣepe nipa ofin: emi kò sá ti mọ̀ ojukokoro, bikoṣe bi ofin ti wipe, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro. 8 Ẹ̀ṣẹ si ti ipa ofin ri aye, o ṣiṣẹ onirũru ifẹkufẹ ninu mi. Nitori laisi ofin, ẹ̀ṣẹ kú. 9 Emi si ti wà lãye laisi ofin nigbakan rì: ṣugbọn nigbati ofin de, ẹ̀ṣẹ sọji, emi si kú. 10 Ofin ti a ṣe fun ìye, eyi li emi si wa ri pe o jẹ fun ikú. 11 Nitori ẹ̀ṣẹ ti ipa ofin ri aye, o tàn mi jẹ, o si ti ipa rẹ̀ lù mi pa. 12 Bẹ̃ni mimọ́ li ofin, mimọ́ si li aṣẹ, ati ododo, ati didara. 13 Njẹ ohun ti o dara ha di ikú fun mi bi? Ki a má ri. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ ki o le farahan bi ẹ̀ṣẹ o nti ipa ohun ti o dara ṣiṣẹ́ ikú ninu mi, ki ẹ̀ṣẹ le ti ipa ofin di buburu rekọja.

Ogun Tí Ń Jà Ninu Eniyan

14 Nitori awa mọ̀ pe ohun ẹmí li ofin: ṣugbọn ẹni ti ara li emi, ti a ti tà sabẹ ofin. 15 Nitori ohun ti emi nṣe, emi kò mọ̀: nitori ki iṣe ohun ti mo fẹ li emi nṣe; ṣugbọn ohun ti mo korira, li emi nṣe. 16 Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ eyini li emi nṣe, mo gba pe ofin dara. 17 Njẹ nisisiyi kì iṣe emi li o nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti o ngbe inu mi. 18 Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri. 19 Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe. 20 Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti ngbe inu mi. 21 Njẹ mo ri niti ofin pe, bi emi ti nfẹ lati mã ṣe rere, buburu a ma wà lọdọ mi. 22 Inu mi sá dùn si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu: 23 Ṣugbọn mo ri ofin miran ninu awọn ẹ̀ya ara mi, ti mba ofin inu mi jagun ti o si ndì mi ni igbekun wá fun ofin ẹ̀ṣẹ, ti o mbẹ ninu awọn ẹ̀ya ara mi. 24 Emi ẹni òṣi! tani yio gbà mi lọwọ ara ikú yi? 25 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa. Njẹ nitorina emi tikarami nfi inu jọsin fun ofin Ọlọrun; ṣugbọn mo nfi ara jọsin fun ofin ẹ̀ṣẹ.

Romu 8

Ìgbésí-Ayé Onigbagbọ Ninu Ẹ̀mí

1 NJẸ ẹbi kò si nisisiyi fun awọn ti o wà ninu Kristi Jesu, awọn ti kò rìn nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. 2 Nitori ofin Ẹmí ìye ninu Kristi Jesu ti sọ mi di omnira lọwọ ofin ẹ̀ṣẹ ati ti ikú. 3 Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara: 4 Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. 5 Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, nwọn a mã ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmí, nwọn a mã ro ohun ti Ẹmí. 6 Nitori ero ti ara ikú ni; ṣugbọn ero ti Ẹmí ni iye ati alafia: 7 Nitori ero ti ara ọtá ni si Ọlọrun: nitori ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò tilẹ le ṣe e. 8 Bẹ̃li awọn ti o wà ninu ti ara, kò le wù Ọlọrun. 9 Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀. 10 Bi Kristi ba si wà ninu nyin, ara jẹ okú nitori ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn ẹmí jẹ iyè nitori ododo. 11 Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu. 12 Njẹ nitorina, ara, ajigbèsè li awa, ki iṣe ara li a jẹ ni gbese, ti a o fi mã wà nipa ti ara. 13 Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmí bi ẹnyin ba npa iṣẹ́ ti ara run, ẹnyin ó yè. 14 Nitori iye awọn ti a nṣe amọ̀na fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun. 15 Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba. 16 Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe: 17 Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.

Ògo Ayé Tí ń Bọ̀

18 Nitori mo ṣíro rẹ̀ pe, ìya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa. 19 Nitori ifojusọ́na ti ẹda nduro dè ifihàn awọn ọmọ Ọlọrun. 20 Nitori a tẹri ẹda ba fun asan, ki iṣe ifẹ rẹ̀, ṣugbọn nitori ẹniti o tẹ ori rẹ̀ ba, ni ireti, 21 Nitori a ó sọ ẹda tikalarẹ di omnira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si omnira ogo awọn ọmọ Ọlọrun. 22 Nitori awa mọ̀ pe gbogbo ẹda li o jumọ nkerora ti o si nrọbi pọ̀ titi di isisiyi. 23 Kì si iṣe awọn nikan, ṣugbọn awa tikarawa pẹlu, ti o ni akọ́so Ẹmí, ani awa tikarawa nkerora ninu ara wa, awa nduro dè isọdọmọ, ani idande ara wa. 24 Nitori ireti li a fi gbà wa là: ṣugbọn ireti ti a bá ri kì iṣe ireti: nitori tani nreti ohun ti o bá ri? 25 Ṣugbọn bi awa ba nreti eyi ti awa kò ri, njẹ awa nfi sũru duro dè e. 26 Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa. 27 Ẹniti o si nwá inu ọkàn wo, o mọ̀ ohun ti inu Ẹmí, nitoriti o mbẹbẹ fun awọn enia mimọ́ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun. 28 Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀. 29 Nitori awọn ẹniti o ti mọ̀ tẹlẹ, li o si ti yàn tẹlẹ lati ri bi aworan Ọmọ rẹ̀, ki on le jẹ akọbi larin awọn arakunrin pupọ. 30 Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo.

Ìfẹ́ Ọlọrun Sí Wa Nípa Jesu

31 Njẹ kili awa o ha wi si nkan wọnyi? Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa? 32 Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ? 33 Tani yio ha kà ohunkohun si ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ihaṣe Ọlọrun ti ndare? 34 Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa? 35 Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi ìyan, tabi ìhoho, tabi ewu, tabi idà? 36 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori rẹ li a ṣe npa wa kú li gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa. 37 Ṣugbọn ninu gbogbo nkan wọnyi awa jù ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa. 38 Nitori o da mi loju pe, kì iṣe ikú, tabi ìye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun ìgba isisiyi, tabi ohun ìgba ti mbọ̀, 39 Tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

Romu 9

Ọlọrun Yan Israẹli

1 OTITỌ li emi nsọ ninu Kristi, emi kò ṣeke, ọkàn mi si njẹ mi li ẹrí ninu Ẹmí Mimọ́, 2 Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi. 3 Nitori mo fẹrẹ le gbadura pe ki a ké emi tikarami kuro lọdọ Kristi, nitori awọn ará mi, awọn ibatan mi nipa ti ara: 4 Awọn ẹniti iṣe Israeli; ti awọn ẹniti isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati ìsin Ọlọrun, ati awọn ileri; 5 Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin. 6 Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli: 7 Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, Ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ. 8 Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ. 9 Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin. 10 Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa; 11 Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;) 12 A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo, 13 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira. 14 Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri. 15 Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun. 16 Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu. 17 Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. 18 Nitorina li o ṣe nṣãnu fun ẹniti o wù u, ẹniti o wù u a si mu u li ọkàn le.

Ibinu Ọlọrun ati Àánú Rẹ̀

19 Iwọ o si wi fun mi pe, Kili ó ha tun ba ni wi si? Nitori tali o ndè ifẹ rẹ̀ lọ̀na? 20 Bẹ̃kọ, iwọ enia, tani iwọ ti nda Ọlọrun lohùn? Ohun ti a mọ a ha mã wi fun ẹniti ti o mọ ọ pé, Ẽṣe ti iwọ fi mọ mi bayi? 21 Amọ̀koko kò ha li agbara lori amọ̀, ninu ìṣu kanna lati ṣe apakan li ohun elo si ọlá, ati apakan li ohun elo si ailọlá? 22 Njẹ bi Ọlọrun ba fẹ fi ibinu rẹ̀ hàn nkọ, ti o si fẹ sọ agbara rẹ̀ di mimọ̀, ti o si mu suru pupọ fun awọn ohun elo ibinu ti a ṣe fun iparun; 23 Ati ki o le sọ ọrọ̀ ogo rẹ̀ di mimọ̀ lara awọn ohun elo ãnu ti o ti pèse ṣaju fun ogo, 24 Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu? 25 Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ. 26 Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye. 27 Isaiah si kigbe nitori Israeli pe, Bi iye awọn ọmọ Israeli bá ri bi iyanrin okun, apakan li a ó gbala. 28 Nitori Oluwa yio mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ lori ilẹ aiye, yio pari rẹ̀, yio si ke e kúru li ododo. 29 Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora.

Ìyìn Rere Náà Wà Fún Israẹli Pẹlu

30 Njẹ kili awa o ha wi? Pe awọn Keferi, ti kò lepa ododo, ọwọ́ wọn tẹ̀ ododo, ṣugbọn ododo ti o ti inu igbala wá ni. 31 Ṣugbọn Israeli ti nlepa ofin ododo, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ ofin ododo. 32 Nitori kini? nitori nwọn ko wá a nipa igbagbọ́, ṣugbọn bi ẹnipe nipa iṣẹ ofin. Nitori nwọn kọsẹ lara okuta ikọsẹ ni; 33 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kiyesi i, mo gbé okuta ikọsẹ ati àpata idugbolu kalẹ ni Sioni: ẹnikẹni ti o ba si gbà a gbọ, oju kì yio ti i.

Romu 10

1 ARÁ, ifẹ ọkàn mi ati adura mi si Ọlọrun fun Israeli ni, fun igbala wọn. 2 Nitori mo gbà ẹri wọn jẹ pe, nwọn ni itara fun Ọlọrun, ṣugbọn kì iṣe gẹgẹ bi ìmọ. 3 Nitori bi nwọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti nwọn si nwá ọna lati gbé ododo ara wọn kalẹ, nwọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun. 4 Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́.

Ìgbàlà Fún Gbogbo Eniyan

5 Mose sá kọ̀we rẹ̀ pe, ẹniti o ba ṣe ododo ti iṣe ti ofin, yio yè nipa rẹ̀. 6 Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:) 7 Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá). 8 Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu; 9 Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. 10 Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala. 11 Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i. 12 Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l'Oluwa gbogbo wọn, o si pọ̀ li ọrọ̀ fun gbogbo awọn ti nkepè e. 13 Nitori ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ, Oluwa, li a o gbàlà. 14 Njẹ nwọn o ha ti ṣe kepe ẹniti nwọn kò gbagbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbà ẹniti nwọn kò gburó rẹ̀ rí gbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbọ́ laisi oniwasu? 15 Nwọn o ha si ti ṣe wasu, bikoṣepe a rán wọn? gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹsẹ awọn ti nwasu ihinrere alafia ti dara to, awọn ti nwãsu ihin ayọ̀ ohun rere! 16 Ṣugbọn ki iṣe gbogbo wọn li o gbọ́ ti ihinrere. Nitori Isaiah wipe, Oluwa, tali o gbà ihin wa gbọ́? 17 Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ́ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọ̀rọ Ọlọrun. 18 Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye. 19 Ṣugbọn mo ni, Israeli kò ha mọ̀ bi? Mose li o kọ́ wipe, Emi o fi awọn ti kì iṣe enia mu nyin jowú, ati awọn alaimoye enia li emi o fi bi nyin ninu. 20 Ṣugbọn Isaiah tilẹ laiya, o si wipe, Awọn ti kò wá mi ri mi; awọn ti kò bère mi li a fi mi hàn fun. 21 Ṣugbọn nipa ti Israeli li o wipe, Ni gbogbo ọjọ ni mo nà ọwọ́ mi si awọn alaigbọran ati alariwisi enia.

Romu 11

Àánú Ọlọrun Fún Israẹli

1 NJẸ mo ni, Ọlọrun ha ta awọn enia rẹ̀ nù bi? Ki a má ri. Nitori Israeli li emi pẹlu, lati inu irú-ọmọ Abrahamu, li ẹ̀ya Benjamini. 2 Ọlọrun kò ta awọn enia rẹ̀ nù ti o ti mọ̀ tẹlẹ. Tabi ẹnyin kò mọ̀ bi iwe-mimọ́ ti wi niti Elijah? bi o ti mbẹ̀bẹ lọdọ Ọlọrun si Israeli, wipe, 3 Oluwa, nwọn ti pa awọn woli rẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ; emi nikanṣoṣo li o si kù, nwọn si nwá ẹmí mi. 4 Ṣugbọn idahun wo li Ọlọrun fifun u? Mo ti kù ẹ̃dẹ́gbãrin enia silẹ fun ara mi, awọn ti kò tẹ ẽkun ba fun Baali. 5 Gẹgẹ bẹ̃ si ni li akokò isisiyi pẹlu, apakan wà nipa iyanfẹ ti ore-ọfẹ. 6 Bi o ba si ṣepe nipa ti ore-ọfẹ ni, njẹ kì iṣe ti iṣẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, ore-ọfẹ kì iṣe ore-ọfẹ mọ́. Ṣugbọn biobaṣepe nipa ti iṣẹ́ ni, njẹ kì iṣe ti ore-ọfẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, iṣẹ kì iṣe iṣẹ mọ́. 7 Ki ha ni? ohun ti Israeli nwá kiri, on na ni kò ri; ṣugbọn awọn ẹni iyanfẹ ti ri i, a si sé aiya awọn iyokù le: 8 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ọlọrun ti fun wọn li ẹmí orun: oju ki nwọn ki o má le woran, ati etí ki nwọn ki o má le gbọran, titi o fi di oni-oloni. 9 Dafidi si wipe, Jẹ ki tabili wọn ki o di idẹkun, ati ẹgẹ́, ati ohun ikọsẹ, ati ẹsan fun wọn: 10 Ki oju wọn ki o ṣokun, ki nwọn ki o má le riran, ki o si tẹ̀ ẹhin wọn ba nigbagbogbo. 11 Njẹ mo ni, Nwọn ha kọsẹ̀ ki nwọn ki o le ṣubu? Ki a má ri: ṣugbọn nipa iṣubu wọn, igbala dé ọdọ awọn Keferi, lati mu wọn jowú. 12 Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ̀ aiye, ati bi ifasẹhin wọn ba di ọrọ̀ awọn Keferi; melomelo ni kíkún wọn?

Ìgbàlà fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Kì Í Ṣe Juu

13 Ẹnyin ti iṣe Keferi li emi sa mba sọrọ, niwọnbi emi ti jẹ aposteli awọn Keferi, mo gbé oyè mi ga: 14 Bi o le ṣe ki emi ki o le mu awọn ará mi jowú, ati ki emi ki o le gbà diẹ là ninu wọn. 15 Nitori bi titanù wọn ba jẹ ìlaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú? 16 Njẹ bi akọso ba mọ́, bẹ̃li akopọ: bi gbòngbo ba si mọ́, bẹ si li awọn ẹ̀ka rẹ̀ na. 17 Ṣugbọn bi a ba yà ninu awọn ẹ̀ka kuro, ti a si lọ́ iwọ, ti iṣe igi oróro igbẹ́ sara wọn, ti iwọ si mba wọn pín ninu gbòngbo ati ọra igi oróro na; 18 Máṣe ṣe fefé si awọn ẹ̀ka na. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe fefé, iwọ kọ́ li o rù gbòngbo, ṣugbọn gbòngbo li o rù iwọ. 19 Njẹ iwọ o wipe, A ti fà awọn ẹ̀ka na ya, nitori ki a le lọ́ mi sinu rẹ̀. 20 O dara; nitori aigbagbọ́ li a ṣe fà wọn ya kuro, iwọ si duro nipa igbagbọ́ rẹ. Máṣe gbé ara rẹ ga, ṣugbọn bẹ̀ru: 21 Nitori bi Ọlọrun kò ba da ẹ̀ka-iyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si. 22 Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ̀: ki a má ba ke iwọ na kuro. 23 Ati awọn pẹlu, bi nwọn kò ba joko sinu aigbagbọ́, a o lọ́ wọn sinu rẹ̀: nitori Ọlọrun le tún wọn lọ́ sinu rẹ̀. 24 Nitori bi a ti ke iwọ kuro lara igi oróro igbẹ́ nipa ẹda, ti a si lọ́ iwọ sinu igi oróro rere lodi si ti ẹda: melomelo li a o lọ́ awọn wọnyi, ti iṣe ẹka-iyẹka sara igi oróro wọn?

Àánú Ọlọrun Wà fún Gbogbo Eniyan

25 Ará, emi kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li òpe niti ohun ijinlẹ yi, ki ẹnyin má ba ṣe ọlọ́gbọn li oju ara nyin; pe ifọju bá Israeli li apakan, titi kíkún awọn Keferi yio fi de. 26 Bẹ̃li a o si gbà gbogbo Israeli là; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ni Sioni li Olugbala yio ti jade wá, yio si yi aiwa-bi-Ọlọrun kuro lọdọ Jakọbu: 27 Eyi si ni majẹmu mi fun wọn, nigbati emi o mu ẹ̀ṣẹ wọn kuro. 28 Nipa ti ihinrere, ọtá ni nwọn nitori nyin: bi o si ṣe ti iyanfẹ ni, olufẹ ni nwọn nitori ti awọn baba. 29 Nitori ailábámọ̀ li ẹ̀bun ati ipe Ọlọrun. 30 Nitori gẹgẹ bi ẹnyin kò ti gbà Ọlọrun gbọ́ ri, ṣugbọn nisisiyi ti ẹnyin ri ãnu gbà nipa aigbagbọ́ wọn: 31 Gẹgẹ bẹ̃li awọn wọnyi ti o ṣe aigbọran nisisiyi, ki awọn pẹlu ba le ri ãnu gbà nipa ãnu ti a fi hàn nyin. 32 Nitori Ọlọrun sé gbogbo wọn mọ pọ̀ sinu aigbagbọ́, ki o le ṣãnu fun gbogbo wọn.

Ìyìn fún Ọlọrun

33 Ã! ijinlẹ ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ Ọlọrun! awamáridi idajọ rẹ̀ ti ri, ọ̀na rẹ̀ si jù awari lọ! 34 Nitori tali o mọ̀ inu Oluwa? tabi tani iṣe ìgbimọ rẹ̀? 35 Tabi tali o kọ́ fifun u, ti a o si san a pada fun u? 36 Nitori lati ọdọ rẹ̀, ati nipa rẹ̀, ati fun u li ohun gbogbo: ẹniti ogo wà fun lailai. Amin.

Romu 12

Ayé Titun Ninu Kristi

1 NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na. 2 Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé. 3 Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wà ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o máṣe rò ara rẹ̀ jù bi o ti yẹ ni rirò lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntun-wọnsìn, bi Ọlọrun ti fi ìwọn igbagbọ́ fun olukuluku. 4 Nitori gẹgẹ bi awa ti li ẹ̀ya pipọ ninu ara kan, ti gbogbo ẹ̀ya kò si ni iṣẹ kanna: 5 Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀. 6 Njẹ bi awa si ti nri ọ̀tọ ọ̀tọ ẹ̀bun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a mã sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọn igbagbọ́; 7 Tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹniti nkọ́ni, ki o kọjusi kíkọ́; 8 Tabi ẹniti o ngbàni niyanju, si igbiyanju: ẹniti o nfi funni ki o mã fi inu kan ṣe e; ẹniti nṣe olori, ki o mã ṣe e li oju mejeji; ẹniti nṣãnu, ki o mã fi inu didùn ṣe e.

Àwọn Ìlànà fún Ìgbésí-Ayé Onigbagbọ

9 Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere. 10 Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju. 11 Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa; 12 Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura; 13 Ẹ mã pese fun aini awọn enia mimọ́; ẹ fi ara nyin fun alejò iṣe. 14 Ẹ mã súre fun awọn ti nṣe inunibini si nyin: ẹ mã sure, ẹ má si ṣepè. 15 Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun. 16 Ẹ mã wà ni inu kanna si ara nyin. Ẹ máṣe tọju ohun gíga, ṣugbọn ẹ mã tẹle awọn onirẹlẹ. Ẹ máṣe jẹ ọlọ́gbọn li oju ara nyin. 17 Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. Ẹ mã pèse ohun ti o tọ́ niwaju gbogbo enia. 18 Bi o le ṣe, bi o ti wà ni ipa ti nyin, ẹ mã wà li alafia pẹlu gbogbo enia. 19 Olufẹ, ẹ máṣe gbẹsan ara nyin, ṣugbọn ẹ fi àye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan. 20 Ṣugbọn bi ebi ba npa ọtá rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba ngbẹ ẹ, fun u li omi mu: ni ṣiṣe bẹ̃ iwọ ó kó ẹyín ina le e li ori. 21 Maṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu.

Romu 13

Ipò Àwọn Aláṣẹ Ìlú

1 KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá. 2 Nitorina ẹniti o ba tapá si aṣẹ, o tapá si ìlana Ọlọrun: awọn ẹniti o ba si ntapá, yio gbà ẹbi fun ara wọn. 3 Nitori awọn ijoye kì iṣe ẹ̀ru si iṣẹ rere, bikoṣe si iṣẹ buburu. Njẹ iwọ ha fẹ ṣaibẹru aṣẹ wọn? ṣe eyi ti o dara, iwọ ó si gbà iyìn lati ọdọ rẹ̀: 4 Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe si ọ fun rere. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe buburu, bẹru; nitori kò gbé idà na lasan: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe, olugbẹsan lati ṣiṣẹ ibinu lara ẹniti nṣe buburu. 5 Nitorina ẹnyin kò gbọdọ ṣaima tẹriba, kì iṣe nitoriti ibinu nikan, ṣugbọn nitori ẹri-ọkàn pẹlu. 6 Nitori idi eyi na li ẹ ṣe san owo-ode pẹlu: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni nwọn eyiyi na ni nwọn mbojuto nigbagbogbo. 7 Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀ru fun ẹniti ẹ̀ru iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀.

Ìfẹ́ Láàrin Àwọn Onigbagbọ

8 Ẹ máṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣepe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni: nitori ẹniti o ba fẹran ọmọnikeji rẹ̀, o kó ofin já. 9 Nitori eyi, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, Iwọ kò gbọdọ pania, Iwọ kò gbọdọ jale, Iwọ kò gbọdọ jẹri eke, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro; bi ofin miran ba si wà, a ko o pọ ninu ọ̀rọ yi pe, Fẹran ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. 10 Ifẹ kì iṣe ohun buburu si ọmọnikeji rẹ̀: nitorina ifẹ li akója ofin.

Ọjọ́ Oluwa Fẹ́rẹ̀ Dé

11 Ati eyi, bi ẹ ti mọ̀ akokò pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile jù igbati awa ti gbagbọ́ lọ. 12 Oru bukọja tan, ilẹ si fẹrẹ mọ́: nitorina ẹ jẹ ki a bọ́ ara iṣẹ òkunkun silẹ, ki a si gbe ihamọra imọlẹ wọ̀. 13 Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara. 14 Ṣugbọn ẹ gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ki ẹ má si pèse fun ara, lati mã mu ifẹkufẹ rẹ̀ ṣẹ.

Romu 14

Má Ṣe Dá Ẹnìkejì Rẹ Lẹ́jọ́

1 ṢUGBỌN ẹniti o ba ṣe ailera ni igbagbọ́ ẹ gbà a, li aitọpinpin iṣiyemeji rẹ̀. 2 Ẹnikan gbagbọ́ pe on le mã jẹ ohun gbogbo: ẹlomiran ti o si ṣe alailera njẹ ewebẹ. 3 Ki ẹniti njẹ máṣe kẹgan ẹniti kò jẹ; ki ẹniti kò si jẹ ki o máṣe dá ẹniti njẹ lẹjọ: nitori Ọlọrun ti gbà a. 4 Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro. 5 Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rẹ̀ loju ni inu ara rẹ̀. 6 Ẹniti o ba nkiyesi ọjọ, o nkiyesi i fun Oluwa; ẹniti kò ba si kiyesi ọjọ, fun Oluwa ni kò kiyesi i. Ẹniti njẹun, o njẹun fun Oluwa, nitori o ndupẹ lọwọ Ọlọrun; ẹniti kò ba si jẹun, fun Oluwa ni kò jẹun, o si ndupẹ lọwọ Ọlọrun. 7 Nitori kò si ẹnikan ninu wa ti o wà lãye fun ara rẹ̀, kò si si ẹniti o nkú fun ara rẹ̀. 8 Nitori bi a ba wà lãye, awa wà lãye fun Oluwa; bi a ba si kú, awa kú fun Oluwa: nitorina bi a wà lãye, tabi bi a kú ni, ti Oluwa li awa iṣe. 9 Nitori idi eyi na ni Kristi ṣe kú, ti o si tún yè, ki o le jẹ Oluwa ati okú ati alãye. 10 Ṣugbọn ẽṣe ti iwọ fi nda arakunrin rẹ lẹjọ? tabi ẽsitiṣe ti iwọ fi nkẹgan arakunrin rẹ? gbogbo wa ni yio sá duro niwaju itẹ́ idajọ Kristi. 11 Nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Bi emi ti wà, gbogbo ẽkún ni yio kunlẹ fun mi, ati gbogbo ahọn ni yio si jẹwọ fun Ọlọrun. 12 Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun.

Ẹ Má Mú Arakunrin Yín Kọsẹ̀

13 Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀. 14 Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun. 15 Ṣugbọn bi inu arakunrin rẹ ba bajẹ nitori onjẹ rẹ, njẹ iwọ kò rìn ninu ifẹ mọ́. Ẹniti Kristi kú fun, máṣe fi onjẹ rẹ pa a kúgbe. 16 Njẹ ẹ máṣe jẹ ki a mã sọ̀rọ ire nyin ni buburu. 17 Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́. 18 Nitori ẹniti o ba nsìn Kristi ninu nkan wọnyi, li o ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun, ti o si ni iyin lọdọ enia. 19 Njẹ nitorina, ki awa ki o mã lepa ohun ti iṣe ti alafia, ati ohun ti awa o fi gbe ara wa ró. 20 Nitori onjẹ máṣe bi iṣẹ Ọlọrun ṣubu. Ohun gbogbo li o mọ́ nitõtọ; ṣugbọn ibi ni fun oluwarẹ̀ na ti o njẹun lọna ikọsẹ. 21 O dara ki a má tilẹ jẹ ẹran, ki a má mu waini, ati ohun kan nipa eyi ti arakunrin rẹ yio kọsẹ, ati ti a o si fi sọ ọ di alailera. 22 Iwọ ní igbagbọ́ bi? ní i fun ara rẹ niwaju Ọlọrun. Alabukun-fun ni oluwarẹ̀ na ti ko da ara rẹ̀ lẹbi ninu ohun ti o yàn. 23 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣiyemeji, o jẹbi bi o ba jẹ, nitoriti kò ti inu igbagbọ́ wá: ati ohunkohun ti kò ti inu igbagbọ wá, ẹṣẹ ni.

Romu 15

Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ó Tẹ́ Ẹlòmíràn Lọ́rùn

1 NJẸ o yẹ ki awa ti o lera iba mã ru ẹrù ailera awọn alailera, ki a má si ṣe ohun ti o wù ara wa. 2 Jẹ ki olukuluku wa ki o mã ṣe ohun ti o wù ọmọnikeji rẹ̀ si rere rẹ̀ lati gbe e ró. 3 Nitori Kristi pẹlu kò ṣe ohun ti o wù ara rẹ̀; ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹ̀gan awọn ti ngàn ọ ṣubu lù mi. 4 Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ fun kíkọ wa, pe nipa sũru ati itunu iwe-mimọ́ ki a le ni ireti. 5 Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu: 6 Ki ẹnyin ki o le fi ọkàn kan ati ẹnu kan yìn Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa, logo.

Bákan Náà Ni Ìyìn Rere Fún Juu Ati Fún Giriki

7 Nitorina ẹ gbá ara nyin mọra, gẹgẹ bi Kristi ti gbá wa mọra fun ogo Ọlọrun. 8 Mo si wipe, a ti fi Jesu Kristi ṣe iranṣẹ ikọla nitori otitọ Ọlọrun, ki o ba le mu awọn ileri na duro ti a ti ṣe fun awọn baba, 9 Ati ki awọn Keferi ki o le yìn Ọlọrun logo nitori ãnu rẹ̀; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori eyi li emi ó ṣe yin ọ lãrin awọn Keferi, emi o si kọrin si orukọ rẹ. 10 O si tún wipe, Ẹnyin Keferi, ẹ mã yọ̀ pẹlu awọn enia rẹ̀. 11 Ati pẹlu, Ẹ yìn Oluwa gbogbo ẹnyin Keferi; ẹ si kokikí rẹ̀, ẹnyin enia gbogbo. 12 Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si. 13 Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́.

Iṣẹ́ Ìyìn Rere Paulu

14 Ará mi, o si da emi tikarami loju nipa ti nyin pe, ẹnyin si kun fun ore, a si fi gbogbo imọ kún nyin, ẹnyin si le mã kìlọ fun ara nyin. 15 Ṣugbọn, ará mi, mo fi igboiya kọwe si nyin li ọna kan, bi ẹni tun nrán nyin leti, nitori ore-ọfẹ ti a ti fifun mi lati ọdọ Ọlọrun wá, 16 Ki emi ki o le ṣe iranṣẹ Jesu Kristi si awọn Keferi, lati ta ọrẹ ihinrere Ọlọrun, ki ọrẹ awọn Keferi ki o le di itẹwọgbà, ti a sọ di mimọ́ nipa Ẹmí Mimọ́. 17 Nitorina mo ni iṣogo ninu Jesu Kristi nipa ohun ti iṣe ti Ọlọrun. 18 Emi kò sá gbọdọ sọ ohun kan ninu eyi ti Kristi kò ti ọwọ́ ṣe, si igbọran awọn Keferi nipa ọ̀rọ ati iṣe, 19 Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, nipa agbara Ẹmí Ọlọrun; tobẹ̃ lati Jerusalemu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun. 20 Mo du u lati mã wasu ihinrere na, kì iṣe nibiti a gbé ti da orukọ Kristi ri, ki emi ki o máṣe mọ amọle lori ipilẹ ẹlomiran. 21 Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Awọn ẹniti a kò ti sọ̀rọ rẹ̀ fun, nwọn ó ri i: ati awọn ti kò ti gbọ́, òye yio yé wọn.

Paulu Ṣe Ètò Láti Lọ Sí Romu

22 Nitorina pẹlu li àye ṣe há fun mi li akoko wọnyi lati tọ̀ nyin wá. 23 Ṣugbọn nisisiyi bi emi kò ti li àye mọ́ li ẹkùn wọnyi, bi emi si ti fẹ gidigidi lati ọdún melo wọnyi lati tọ̀ nyin wá, 24 Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan. 25 Ṣugbọn nisisiyi mo nlọ si Jerusalemu lati ṣe iranṣẹ fun awọn enia mimọ́. 26 Nitoriti o wù awọn ará Makedonia ati Akaia lati da owo jọ fun awọn talakà awọn enia mimọ́ ti o wà ni Jerusalemu. 27 Nitõtọ ifẹ inu rere wọn ni; ajigbese wọn ni nwọn sá ṣe. Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn Keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmí wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ. 28 Nitorina nigbati mo ba ti ṣe eyi tan, ti mo ba si ti dí èdidi eso yi fun wọn tan, emi ó ti ọdọ nyin lọ si Spania. 29 Mo si mọ pe, nigbati mo ba de ọdọ nyin, emi o wá ni kikún ibukún ihinrere Kristi. 30 Mo si bẹ̀ nyin, ará, nitori Oluwa wa Jesu Kristi, ati nitori ifẹ Ẹmí, ki ẹnyin ki o ba mi lakaka ninu adura nyin si Ọlọrun fun mi; 31 Ki a le gbà mi lọwọ awọn alaigbọran ni Judea ati ki iṣẹ-iranṣẹ ti mo ni si Jerusalemu le jẹ itẹwọgbà lọdọ awọn enia mimọ́. 32 Ki emi ki o le fi ayọ̀ tọ̀ nyin wá nipa ifẹ Ọlọrun, ati ki emi le ni itura pọ pẹlu nyin. 33 Njẹ ki Ọlọrun alafia ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Romu 16

Paulu Kí Ọpọlọpọ Eniyan Ninu Ìjọ Romu

1 MO fi Febe, arabinrin wa, le nyin lọwọ ẹniti iṣe diakoni ijọ ti o wà ni Kenkrea: 2 Ki ẹnyin le gbà a ninu Oluwa, bi o ti yẹ fun awọn enia mimọ́, ki ẹnyin ki o si ràn a lọwọ iṣẹkiṣẹ ti o nwá ni iranlọwọ lọdọ nyin: nitori on pẹlu ti nṣe oluranlọwọ fun ẹni pipọ, ati fun emi na pẹlu. 3 Ẹ kí Priskilla ati Akuila, awọn alabaṣiṣẹ mi ninu Kristi Jesu: 4 Awọn ẹniti, nitori ẹmí mi, nwọn fi ọrùn wọn lelẹ: fun awọn ẹniti kì iṣe kiki emi nikan li o ndupẹ, ṣugbọn gbogbo ijọ larin awọn Keferi pẹlu. 5 Ẹ si kí ijọ ti o wà ni ile wọn. Ẹ ki Epenetu, olufẹ mi ọwọn, ẹniti iṣe akọso Asia fun Kristi. 6 Ẹ kí Maria, ti o ṣe lãla pipọ lori wa. 7 Ẹ kí Androniku ati Junia, awọn ibatan mi, ati awọn ẹgbẹ mi ninu tubu, awọn ẹniti o ni iyìn lọdọ awọn Aposteli, awọn ẹniti o ti wà ninu Kristi ṣaju mi pẹlu. 8 Ẹ kí Ampliatu olufẹ mi ninu Oluwa. 9 Ẹ kí Urbani, alabaṣiṣẹ wa ninu Kristi, ati Staki olufẹ mi. 10 Ẹ ki Apelle ẹniti a mọ̀ daju ninu Kristi. Ẹ kí awọn arãle Aristobulu. 11 Ẹ kí Herodioni, ibatan mi. Ẹ kí awọn arãle Narkissu, ti o wà ninu Oluwa. 12 Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa. 13 Ẹ kí Rufu ti a yàn ninu Oluwa, ati iya rẹ̀ ati ti emi. 14 Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Herme, ati awọn arakunrin ti o wà pẹlu wọn. 15 Ẹ kí Filologu, ati Julia, Nereu, ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa, ati gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà pẹlu wọn. 16 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ ki ara nyin. Gbogbo ijọ Kristi kí nyin.

Paulu Ṣe Ìkìlọ̀

17 Ará, emi si bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe ìyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ̀ wá lodi si ẹkọ́ ti ẹnyin kọ́; ẹ si kuro ni isọ wọn. 18 Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà. 19 Nitori igbagbọ́ nyin tàn kalẹ de ìbi gbogbo. Nitorina mo ni ayọ̀ lori nyin: ṣugbọn emi fẹ ki ẹ jẹ ọlọgbọn si ohun ti o ṣe rere, ki ẹ si ṣe òpe si ohun ti iṣe buburu. 20 Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin.

Àwọn Tí Ó Wà Lọ́dọ̀ Paulu Kí Ìjọ Romu

21 Timotiu, alabaṣiṣẹ mi, ati Lukiu, ati Jasoni, ati Sosipateru, awọn ibatan mi, ki nyin. 22 Emi Tertiu ti nkọ Episteli yi, kí nyin ninu Oluwa. 23 Gaiu, bãle mi, ati ti gbogbo ijọ, ki nyin. Erastu, olutọju iṣura ilu, kí nyin, ati Kuartu arakunrin. 24 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Oore-ọ̀fẹ́

25 Njẹ fun ẹniti o li agbara lati fi ẹsẹ nyin mulẹ gẹgẹ bi ihinrere mi ati iwasu Jesu Kristi, gẹgẹ bi iṣipaya ohun ijinlẹ, ti a ti pamọ́ lati igba aiyeraiye, 26 Ti a si nfihàn nisisiyi, ati nipa iwe-mimọ́ awọn woli, gẹgẹ bi ofin Ọlọrun aiyeraiye, ti a nfihàn fun gbogbo orilẹ-ède si igbọràn igbagbọ́: 27 Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo nipasẹ Jesu Kristi li ogo wà fun lailai. Amin.

1 Korinti 1

Ìkíni

1 PAULU, ẹniti a pè lati jẹ Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Sostene arakunrin, 2 Si ijọ enia Ọlọrun ti o wà ni Korinti, awọn ti a sọ di mimọ́ ninu Kristi Jesu, awọn ẹniti a npè li enia mimọ́, pẹlu gbogbo awọn ti npè orukọ Jesu Kristi Oluwa wa nibigbogbo, ẹniti iṣe tiwọn ati tiwa: 3 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi.

Ìdúpẹ́

4 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo nitori nyin, nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun nyin ninu Jesu Kristi; 5 Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li a ti sọ nyin di ọlọrọ̀ li ohun gbogbo, ninu ọ̀rọ-isọ gbogbo, ati ninu ìmọ gbogbo; 6 Ani gẹgẹ bi a ti fi idi ẹrí Kristi kalẹ ninu nyin: 7 Tobẹ ti ẹnyin kò fi rẹ̀hin ninu ẹ̀bunkẹbun; ti ẹ si nreti ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi: 8 Ẹniti yio si fi idi nyin kalẹ titi de opin, ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn li ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi. 9 Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.

Ìyapa ninu Ìjọ

10 Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna. 11 Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin. 12 Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi. 13 A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si? 14 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe emi kò baptisi ẹnikẹni ninu nyin, bikoṣe Krispu ati Gaiu; 15 Ki ẹnikẹni ki o máṣe wipe mo ti mbaptisi li orukọ emi tikarami. 16 Mo si baptisi awọn ara ile Stefana pẹlu: lẹhin eyi emi kò mọ̀ bi mo ba baptisi ẹlomiran pẹlu. 17 Nitori Kristi kò rán mi lọ ibaptisi, bikoṣe lati wãsu ihinrere: kì iṣe nipa ọgbọ́n ọ̀rọ, ki a máṣe sọ agbelebu Kristi di alailagbara.

Kristi Ni Agbára ati Ọgbọ́n Ọlọrun

18 Nitoripe wère li ọ̀rọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni. 19 Nitoriti a kọ ọ pe, Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọn run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan. 20 Ọlọ́gbọn na ha da? akọwe na ha da? ojiyan aiye yi na ha da? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n aiye yi di wère? 21 Nitoripe ninu ọgbọ́n Ọlọrun niwọnbi aiye kò ti mọ̀ nitori ọgbọ́n, o wù Ọlọrun nipa wère iwasu lati gbà awọn ti o gbagbọ́ là. 22 Nitoripe awọn Ju mbère àmi, awọn Hellene si nṣafẹri ọgbọ́n: 23 Ṣugbọn awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsẹ̀ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene, 24 Ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọ́n Ọlọrun. 25 Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ. 26 Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè: 27 Ṣugbọn Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara; 28 Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: 29 Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀. 30 Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa: 31 Pe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, Ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

1 Korinti 2

Paulu Ń Waasu Kristi Tí Wọ́n Kàn Mọ́ Agbelebu

1 ATI emi, ará, nigbati mo tọ̀ nyin wá, kì iṣe ọ̀rọ giga ati ọgbọ́n giga ni mo fi tọ̀ nyin wá, nigbati emi nsọ̀rọ ohun ijinlẹ Ọlọrun fun nyin. 2 Nitori mo ti pinnu rẹ̀ pe, emi kì yio mọ̀ ohunkohun larin nyin, bikoṣe Jesu Kristi, ẹniti a kàn mọ agbelebu. 3 Emi si wà pẹlu nyin ni ailera, ati ni ẹ̀ru, ati ni ọ̀pọlọpọ iwarìri. 4 Ati ọ̀rọ mi, ati iwasu mi kì iṣe nipa ọ̀rọ ọgbọ́n enia, ti a fi nyi ni lọkàn pada, bikoṣe nipa ifihan ti Ẹmí ati ti agbara: 5 Ki igbagbọ́ nyin ki o máṣe duro ninu ọgbọ́n enia, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun.

Àṣírí Tí Ẹ̀mí Ọlọrun Fi Hàn

6 Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan: 7 Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa: 8 Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu. 9 Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ. 10 Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun. 11 Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun. 12 Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá. 13 Ohun na ti awa si nsọ, kì iṣe ninu ọ̀rọ ti ọgbọ́n enia nkọ́ni, ṣugbọn eyiti Ẹmí Mimọ́ fi nkọ́ni; eyiti a nfi ohun Ẹmí we ohun Ẹmí. 14 Ṣugbọn enia nipa ti ara kò gbà ohun ti Ẹmí Ọlọrun wọnni: nitoripe wère ni nwọn jasi fun u: on kò si le mọ̀ wọn, nitori nipa ti Ẹmí li a fi nwadi wọn. 15 Ṣugbọn ẹniti o wà nipa ti ẹmí nwadi ohun gbogbo, ṣugbọn kò si ẹnikẹni ti iwadi rẹ̀. 16 Nitoripe tali o mọ̀ inu Oluwa, ti yio fi mã kọ́ ọ? Ṣugbọn awa ni inu Kristi.

1 Korinti 3

Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun

1 ARÁ, emi kò si le ba nyin sọ̀rọ bi awọn ti iṣe ti Ẹmí, bikoṣe bi awọn ti iṣe ti ara, ani bi awọn ọmọ-ọwọ ninu Kristi. 2 Wàra ni mo ti fi bọ́ nyin, kì iṣe onjẹ: nitori ẹ kò iti le gbà a, nisisiyi na ẹ kò iti le gbà a. 3 Nitori ẹnyin jẹ ti ara sibẹ: nitori niwọnbi ilara ati ìja ati ìyapa ba wà larin nyin, ẹnyin kò ha jẹ ti ara ẹ kò ha si nrìn gẹgẹ bi enia? 4 Nitori nigbati ẹnikan nwipe, Emi ni ti Paulu; ti ẹlomiran si nwipe, Emi ni ti Apollo; ẹnyin kò ha iṣe enia bi? 5 Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun. 6 Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá. 7 Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá. 8 Njẹ ẹniti ngbìn, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirẹ̀ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ̀. 9 Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin. 10 Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e. 11 Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi. 12 Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, akekù koriko le ori ipilẹ yi; 13 Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe. 14 Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ̀ ba duro, on ó gbà ère. 15 Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja. 16 Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin? 17 Bi ẹnikan bá ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, on ni Ọlọrun yio parun; nitoripe mimọ́ ni tẹmpili Ọlọrun, eyiti ẹnyin jẹ. 18 Ki ẹnikẹni máṣe tàn ara rẹ̀ jẹ. Bi ẹnikẹni ninu nyin laiye yi ba rò pe on gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, ki o le ba gbọ́n. 19 Nitori ọgbọ́n aiye yi wèrè ni lọdọ Ọlọrun. Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹniti o mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke wọn. 20 A si tún kọ ọ pe, Oluwa mọ̀ ero ironu awọn ọlọgbọ́n pe, asan ni nwọn. 21 Nitorina ki ẹnikẹni máṣe ṣogo ninu enia. Nitori tinyin li ohun gbogbo, 22 Iba ṣe Paulu, tabi Apollo, tabi Kefa, tabi aiye, tabi ìye, tabi ikú, tabi ohun isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ̀; tinyin ni gbogbo wọn; 23 Ẹnyin si ni ti Kristi; Kristi si ni ti Ọlọrun.

1 Korinti 4

Iṣẹ́ Àwọn Aposteli

1 JẸ ki enia ki o ma kà wa bẹ̃ bi iranṣẹ Kristi, ati iriju awọn ohun ijinlẹ Ọlọrun. 2 Pẹlupẹlu a mbere lọwọ iriju pe ki oluwarẹ̀ na ki o jẹ olõtọ. 3 Ṣugbọn, ohun kikini ni fun mi pe, ki ẹ mã ṣe idajọ mi, tabi ki a mã ṣe idajọ mi nipa idajọ enia: nitotọ emi kò ṣe idajọ emi tikarami. 4 Nitoriti emi kò mọ̀ ohunkohun si ara mi; ṣugbọn a kò ti ipa eyi dá mi lare: Ṣugbọn ẹniti nṣe idajọ mi li Oluwa. 5 Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun. 6 Njẹ ará, nkan wọnyi ni mo ti fi ṣe apẹrẹ ara mi ati Apollo nitori nyin; ki ẹnyin ki o le ti ipa wa kọ́ ki ẹ maṣe ré ohun ti a ti kọwe rẹ̀ kọja, ki ẹnikan ninu nyin ki o máṣe ti itori ẹnikan gberaga si ẹnikeji. 7 Nitori tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a? 8 A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin. 9 Nitori mo rò pe Ọlọrun ti yan awa Aposteli kẹhin bi awọn ẹniti a dalẹbi ikú: nitoriti a fi wa ṣe iran wò fun aiye, ati fun angẹli, ati fun enia. 10 Awa jẹ aṣiwere nitori Kristi, ṣugbọn ẹnyin jẹ ọlọgbọ́n ninu Kristi; awa jẹ alailera, ṣugbọn ẹnyin jẹ alagbara; ẹnyin jẹ ọlọlá, ṣugbọn awa jẹ ẹni ẹ̀gan. 11 Ani titi fi di wakati yi li ebi npa wa, ti òrungbẹ si ngbẹ wa, ti a si wà ni ìhoho, ti a si nlù wa, ti a kò si ni ibugbé kan; 12 Ti a nṣe lãlã, a nfi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ: nwọn ngàn wa, awa nsure; nwọn nṣe inunibini si wa, awa nforitì i: 13 Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi. 14 Emi kò kọ̀we nkan wọnyi lati fi dojutì nyin, ṣugbọn lati kìlọ fun nyin bi awọn ọmọ mi ayanfẹ. 15 Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin. 16 Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣe afarawe mi. 17 Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo. 18 Ṣugbọn awọn ẹlomiran gberaga ninu nyin, bi ẹnipe emi kì yio tọ̀ nyin wá mọ́. 19 Ṣugbọn emi ó tọ̀ nyin wá ni lọ̃lọ yi, bi Oluwa ba fẹ; kì si iṣe ọ̀rọ awọn ti ngberaga li emi o mọ̀, bikoṣe agbara. 20 Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe ninu ọ̀rọ, bikoṣe ninu agbara. 21 Kili ẹnyin nfẹ? emi ó ha tọ̀ nyin wá ti emi ti kùmọ bi, tabi ni ifẹ, ati ẹmí inututù?

1 Korinti 5

Paulu Ṣe Ìdájọ́ Lórí Ìwà Ìbàjẹ́

1 A nròhin rẹ̀ kalẹ pe, àgbere wà larin nyin, ati irú àgbere ti a kò tilẹ gburo rẹ̀ larin awọn Keferi, pe ẹnikan ninu nyin fẹ aya baba rẹ̀. 2 Ẹnyin si nfẹ̀ soke, ẹnyin kò kuku kãnu ki a le mu ẹniti o hu iwa yi kuro larin nyin. 3 Nitori lõtọ, bi emi kò ti si lọdọ nyin nipa ti ara, ṣugbọn ti mo wà pẹlu nyin nipa ti ẹmí, mo ti ṣe idajọ ẹniti o hu iwà yi tan, bi ẹnipe mo wà lọdọ nyin. 4 Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa, 5 Ki ẹ fi irú enia bẹ̃ le Satani lọwọ fun iparun ara, ki a le gbà ẹmí là li ọjọ Jesu Oluwa. 6 Iṣeféfe nyin kò dara. Ẹnyin kò mọ̀ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu? 7 Nitorina ẹ mu iwukara atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ́ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ́ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa. 8 Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ. 9 Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn àgbere kẹgbẹ pọ̀: 10 Ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn àgbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukòkoro, tabi awọn alọnilọwọgbà, tabi awọn abọriṣa; nitori nigbana ẹ kò le ṣaima ti aiye kuro. 11 Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun. 12 Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn? 13 Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin.

1 Korinti 6

Onigbagbọ Ń Pe Ara Wọn Lẹ́jọ́ Níwájú Àwọn Alaigbagbọ

1 ẸNIKẸNI ninu nyin, ti o ni ọ̀ran kan si ẹnikeji rẹ̀, ha gbọdọ lọ pè e li ẹjọ niwaju awọn alaiṣõtọ, ki o má si jẹ niwaju awọn enia mimọ́? 2 Ẹnyin kò ha mọ̀ pe awọn enia mimọ́ ni yio ṣe idajọ aiye? Njẹ bi o ba ṣepe a ó tipasẹ nyin ṣe idajọ aiye, ẹnyin ha ṣe alaiyẹ lati ṣe idajọ awọn ọ̀ran ti o kere julọ? 3 E kò mọ̀ pe awa ni yio ṣe idajọ awọn angẹli? melomelo li ohun ti iṣe ti aiye yi? 4 Njẹ bi ẹnyin ni yio ba ṣe idajọ ohun ti iṣe ti aiye yi, ẹnyin ha nyan awọn ti a kò kà si rara ninu ijọ ṣe onidajọ? 5 Mo sọ eyi fun itiju nyin. O ha le jẹ bẹ̃ pe kò si ọlọgbọn kan ninu nyin ti yio le ṣe idajọ larin awọn arakunrin rẹ̀? 6 Ṣugbọn arakunrin npè arakunrin li ẹjọ, ati eyini niwaju awọn alaigbagbọ́. 7 Njẹ nisisiyi, abuku ni fun nyin patapata pe ẹnyin mba ara nyin ṣe ẹjọ. Ẽṣe ti ẹnyin kò kuku gbà ìya? ẽṣe ti ẹnyin kò kuku jẹ ki a rẹ́ nyin jẹ? 8 Ṣugbọn ẹnyin njẹni ni ìya, ẹ sì nrẹ́ ni jẹ, ati eyini awọn arakunrin nyin. 9 Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣõtọ kì yio jogún ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn nyin jẹ: kì iṣe awọn àgbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti nfi ọkunrin bà ara wọn jẹ́, 10 Tabi awọn olè, tabi awọn olojukòkoro, tabi awọn ọmuti, tabi awọn ẹlẹgàn, tabi awọn alọnilọwọgbà ni yio jogún ijọba Ọlọrun. 11 Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.

Ẹ Fi Ara Yín Yin Ọlọrun

12 Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ère: ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn emi kì yio jẹ ki a fi mi sabẹ agbara ohunkohun. 13 Onjẹ fun inu, ati inu fun onjẹ: ṣugbọn Ọlọrun yio fi opin si ati inu ati onjẹ. Ṣugbọn ara kì iṣe ti àgbere, bikoṣe fun Oluwa; ati Oluwa fun ara. 14 Ṣugbọn Ọlọrun ti jí Oluwa dide, yio si jí awa dide pẹlu nipa agbara rẹ̀. 15 Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri. 16 Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan. 17 Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan. 18 Ẹ mã sá fun àgbere. Gbogbo ẹ̀ṣẹ ti enia ndá o wà lode ara; ṣugbọn ẹniti o nṣe àgbere nṣẹ̀ si ara on tikararẹ̀. 19 Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin, 20 Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yìn Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmí nyin, ti iṣe ti Ọlọrun.

1 Korinti 7

Èrò Nípa Igbeyawo

1 NJẸ niti awọn ohun ti ẹ ti kọwe: O dara fun ọkunrin ki o má fi ọwọ kàn obinrin. 2 Ṣugbọn nitori àgbere, ki olukuluku ki o ni aya tirẹ̀, ati ki olukuluku ki o si ni ọkọ tirẹ̀. 3 Ki ọkọ ki o mã ṣe ohun ti o yẹ si aya: bẹ̃ gẹgẹ si li aya pẹlu si ọkọ. 4 Aya kò li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe ọkọ: bẹ̃ gẹgẹ li ọkọ pẹlu kò si li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe aya. 5 Ẹ máṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara nyin, bikoṣe nipa ifimọṣọkan, ki ẹnyin ki o le fi ara nyin fun àwẹ ati adura; ki ẹnyin ki o si tún jùmọ pade, ki Satani ki o máṣe dán nyin wò nitori aimaraduro nyin. 6 Ṣugbọn mo sọ eyi bi imọran, kì iṣe bi aṣẹ. 7 Nitori mo fẹ ki gbogbo enia ki o dabi emi tikarami. Ṣugbọn olukuluku enia ni ẹ̀bun tirẹ̀ lati ọdọ Ọlọrun wá, ọkan bi irú eyi, ati ekeji bi irú eyini. 8 Ṣugbọn mo wi fun awọn apọ́n ati opó pe, O dara fun wọn bi nwọn ba wà gẹgẹ bi emi ti wà. 9 Ṣugbọn bi nwọn kò bá le maraduro, ki nwọn ki o gbeyawo: nitori o san lati gbeyawo jù ati ṣe ifẹkufẹ lọ. 10 Ṣugbọn awọn ti o ti gbeyawo ni mo si paṣẹ fun, ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe Oluwa, Ki aya máṣe fi ọkọ rẹ̀ silẹ. 11 Ṣugbọn bi o bá si fi i silẹ ki o wà li ailọkọ, tabi ki o ba ọkọ rẹ̀ làja: ki ọkọ ki o máṣe kọ̀ aya rẹ̀ silẹ. 12 Ṣugbọn awọn iyokù ni mo wi fun, kì iṣe Oluwa: bi arakunrin kan ba li aya ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe kọ̀ ọ silẹ. 13 Ati obinrin ti o ni ọkọ ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe fi i silẹ. 14 Nitoriti a sọ alaigbagbọ́ ọkọ na di mimọ́ ninu aya rẹ̀, a si sọ alaigbagbọ́ aya na di mimọ́ ninu ọkọ rẹ̀: bikoṣe bẹ̃ awọn ọmọ nyin iba jẹ alaimọ́; ṣugbọn nisisiyi nwọn di mimọ́. 15 Ṣugbọn bi alaigbagbọ́ na ba lọ, jẹ ki o mã lọ. Arakunrin tabi arabinrin kan kò si labẹ ìde, nitori irú ọ̀ran bawọnni: ṣugbọn Ọlọrun pè wa si alafia. 16 Nitori iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ aya, bi iwọ ó gbà ọkọ rẹ là? tabi iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ ọkọ, bi iwọ ó gbà aya rẹ là?

Ipò tí Ọlọrun Yàn fún Ẹnìkọ̀ọ̀kan

17 Ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti pín fun olukuluku enia, bi Oluwa ti pè olukuluku, bẹ̃ni ki o si mã rìn. Bẹ̃ni mo si nṣe ìlana ninu gbogbo ijọ. 18 A ha pè ẹnikan ti o ti kọla? ki o má si ṣe di alaikọla. A ha pè ẹnikan ti kò kọla? ki o máṣe kọla. 19 Ikọla ko jẹ nkan, ati aikọla kò jẹ nkan, bikoṣe pipa ofin Ọlọrun mọ́. 20 Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e. 21 A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini. 22 Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi. 23 A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia. 24 Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun.

Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Tí Kò Tíì Ṣe Igbeyawo ati Àwọn Opó

25 Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo. 26 Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃. 27 A ti dè ọ mọ́ aya ri bi? máṣe wá ọ̀na lati tú kuro. A ti tú ọ kuro lọwọ aya bi? máṣe wá aya ni. 28 Ṣugbọn bi iwọ ba si gbeyawo, iwọ kò dẹṣẹ: bi a ba si gbé wundia ni iyawo, on kò dẹṣẹ. Ṣugbọn irú awọn wọnni yio ni wahalà nipa ti ara: ṣugbọn mo dá nyin si. 29 Ṣugbọn eyi ni mo wi, ará, pe kukuru li akokò: lati isisiyi lọ pe ki awọn ti o li aya ki o dabi ẹnipe nwọn kò ni rí; 30 Ati awọn ti nsọkun, bi ẹ́nipe nwọn kò sọkun rí; ati awọn ti nyọ̀, bi ẹnipe nwọn kò yọ̀ rí; ati awọn ti nrà, bi ẹnipe nwọn kò ni rí; 31 Ati awọn ti nlò ohun aiye yi bi ẹniti kò ṣaṣeju: nitori aṣa aiye yi nkọja lọ. 32 Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa: 33 Ṣugbọn ẹniti o gbeyawo ama ṣe itọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù aya rẹ̀. 34 Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀. 35 Eyi ni mo si nwi fun ère ara nyin; kì iṣe lati dẹkun fun nyin, ṣugbọn nitori eyi ti o tọ́, ati ki ẹnyin ki o le mã sin Oluwa laisi ìyapa-ọkàn. 36 Ṣugbọn bi ẹnikan ba rò pe on kò ṣe ohun ti o yẹ si wundia ọmọbinrin rẹ̀, bi o ba ti di obinrin, bi o ba si tọ bẹ̃, jẹ ki o ṣe bi o ti fẹ, on kò dẹṣẹ: jẹ ki nwọn gbé iyawo. 37 Ṣugbọn ẹniti o duro ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, ti ko ni aigbọdọ máṣe, ṣugbọn ti o li agbara lori ifẹ ara rẹ̀, ti o si ti pinnu li ọkàn rẹ̀ pe, on o pa wundia ọmọbinrin on mọ́, yio ṣe rere. 38 Bẹ̃ si li ẹniti o fi wundia ọmọbinrin funni ni igbeyawo, o ṣe rere: ṣugbọn ẹniti kò fi funni ni igbeyawo ṣe rere jù. 39 A fi ofin dè obinrin niwọn igbati ọkọ rẹ̀ ba wà lãye; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o di omnira lati ba ẹnikẹni ti o wù u gbeyawo; kìki ninu Oluwa. 40 Ṣugbọn gẹgẹ bi imọ̀ mi, alabukun-fun julọ ni bi on ba duro bẹ̃: emi pẹlu si rò pe mo li Ẹmi Ọlọrun.

1 Korinti 8

Oúnjẹ Tí A Fi Rúbọ fún Oriṣa

1 ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro. 2 Bi ẹnikan ba si rò pe on mọ̀ ohun kan, kò ti imọ̀ bi o ti yẹ ti iba mọ̀. 3 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ Ọlọrun, oluwarẹ̀ li o di mimọ̀ fun u. 4 Nitorina niti jijẹ awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe ohun asan li oriṣa li aiye, ati pe kò si Ọlọrun miran bikoṣe ọkanṣoṣo. 5 Nitoripe bi awọn ti a npè li ọlọrun tilẹ wà, iba ṣe li ọrun tabi li aiye (gẹgẹ bi ọ̀pọ ọlọrun ti wà ati ọ̀pọ oluwa,) 6 Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀. 7 Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́. 8 Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju. 9 Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera. 10 Nitoripe bi ẹnikan ba ri ti iwọ ti o ni ìmọ ba joko tì onjẹ ni ile oriṣa, bi on ba ṣe alailera, ọkan rẹ̀ kì yio ha duro lati mã jẹ nkan wọnni ti a fi rubọ si oriṣa? 11 Ati nipa ìmọ rẹ li alailera arakunrin, nitori ẹniti Kristi ṣe kú, yio fi ṣegbé? 12 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣẹ̀ si awọn arakunrin bẹ̃, ti ẹ si npa ọkàn wọn ti iṣe ailera lara, ẹnyin nṣẹ̀ si Kristi. 13 Nitorina, bi onjẹ ba mu arakunrin mi kọsẹ̀, emi kì yio si jẹ ẹran mọ́ titi lai, ki emi má bà mu arakunrin mi kọsẹ̀.

1 Korinti 9

Iṣẹ́ ati Ẹ̀tọ́ Aposteli

1 APOSTELI kọ́ emi iṣe bi? emi kò ha wà li omnira? emi ko ti ri Jesu Kristi Oluwa wa? iṣẹ mi kọ́ ẹnyin iṣe ninu Oluwa? 2 Bi emi ki iṣe Aposteli fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn dajudaju Aposteli li emi iṣe fun nyin: nitori èdidi iṣẹ Aposteli mi li ẹnyin iṣe ninu Oluwa. 3 Èsi mi fun awọn ti nwadi mi li eyi: 4 Awa kò ha li agbara lati mã jẹ ati lati mã mu? 5 Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa? 6 Tabi emi nikan ati Barnaba, awa kò ha li agbara lati joko li aiṣiṣẹ? 7 Tani ilọ si ogun nigba kan rí ni inawo ara rẹ̀? tani igbìn ọgba ajara, ti ki isi jẹ ninu eso rẹ̀? tabi tani mbọ́ ọ̀wọ́-ẹran, ti kì isi jẹ ninu wàra ọ̀wọ́-ẹran na? 8 Emi ha nsọ̀rọ nkan wọnyi bi enia? tabi ofin kò wi bakanna pẹlu bi? 9 Nitoriti a ti kọ ọ ninu ofin Mose pe, Iwọ kò gbọdọ pa malu ti npaka li ẹnu mọ́. Iha ṣe malu li Ọlọrun nṣe itọju bi? 10 Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀. 11 Bi awa ba ti funrugbin ohun ti ẹmí fun nyin, ohun nla ha ni bi awa ó ba ká ohun ti nyin ti iṣe ti ara? 12 Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi. 13 Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ? 14 Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere. 15 Ṣugbọn emi kò lò ọ̀kan ninu nkan wọnyi: bẹ̃li emi kò si kọwe nkan wọnyi, nitori ki a le ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun mi: nitoripe o san fun mi ki emi kuku kú, jù ki ẹnikẹni ki o sọ ogo mi di asan. 16 Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere, emi kò li ohun ti emi ó fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mogbé! bi emi kò ba wasu ihinrere. 17 Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ. 18 Njẹ kini ha li ère mi? pe, nigbati mo ba nwasu ihinrere Kristi fun-ni laini inawo, ki emi ki o máṣe lo agbara mi ninu ihinrere ni kikun. 19 Nitori bi mo ti jẹ omnira kuro lọdọ gbogbo enia, mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo wọn, ki emi ki o le jère pipọ si i. 20 Ati fun awọn Ju mo dabi Ju, ki emi ki o le jère awọn Ju; fun awọn ti mbẹ labẹ ofin, bi ẹniti mbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jère awọn ti mbẹ labẹ ofin; 21 Fun awọn alailofin bi alailofin (emi kì iṣe alailofin si Ọlọrun, ṣugbọn emi mbẹ labẹ ofin si Kristi) ki emi ki o le jère awọn alailofin. 22 Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jère awọn alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo enia, ki emi ki o le gbà diẹ là bi o ti wu ki o ri. 23 Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin. 24 Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nsáre ije, gbogbo nwọn ni nsáre nitõtọ, ṣugbọn ẹnikan ni ngbà ère na? Ẹ sáre bẹ̃, ki ẹnyin ki o le ri gbà. 25 Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ. 26 Nitorina bẹ̃ni emi nsáre, kì iṣe bi ẹniti kò da loju; bẹ̃ni emi njà, ki iṣe bi ẹnikan ti nlu afẹfẹ: 27 Ṣugbọn emi npọn ara mi loju, mo si nmu u wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti wasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikarami máṣe di ẹni itanù.

1 Korinti 10

Ìkìlọ̀ Nípa Ìbọ̀rìṣà

1 NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já; 2 Ti a si baptisi gbogbo wọn si Mose ninu awọsanma ati ninu okun; 3 Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna; 4 Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na. 5 Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù. 6 Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ. 7 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. 8 Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan. 9 Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn. 10 Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn. 11 Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá. 12 Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu. 13 Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a. 14 Nitorina, ẹnyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa. 15 Emi nsọ̀rọ bi ẹnipe fun ọlọgbọn; ẹ gbà eyiti mo wi rò. 16 Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe? 17 Nitoripe awa ti iṣe ọ̀pọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitoripe gbogbo wa li o jumọ npin ninu akara kan nì. 18 Ẹ wo Israeli nipa ti ara: awọn ti njẹ ohun ẹbọ, nwọn ki ha iṣe alabapin pẹpẹ? 19 Njẹ kini mo nwi? pe, ohun ti a fi rubọ si oriṣa jẹ nkan, tabi pe oriṣa jẹ nkan? 20 Ṣugbọn ohun ti mo nwi nipe, ohun ti awọn Keferi fi nrubọ, nwọn fi nrubọ si awọn ẹ̃mi èṣu, kì si iṣe si Ọlọrun: emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ba awọn ẹmi èṣu ṣe ajọpin. 21 Ẹnyin kò le mu ago Oluwa ati ago awọn ẹmi èṣu: ẹnyin kò le ṣe ajọpin ni tabili Oluwa, ati ni tabili awọn ẹmi èṣu. 22 Awa ha nmu Oluwa jowú bi? awa ha li agbara jù u lọ?

Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun

23 Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró. 24 Ki ẹnikẹni máṣe mã wá ti ara rẹ̀, ṣugbọn ki olukuluku mã wá ire ọmọnikeji rẹ̀. 25 Ohunkohun ti a ba ntà li ọjà ni ki ẹ mã jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. 26 Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀. 27 Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. 28 Ṣugbọn bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, A ti fi eyi ṣẹbọ, ẹ máṣe jẹ ẹ nitori ẹniti o fi hàn nyin, ati nitori ẹri-ọkàn (nitoripe ti Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀): 29 Mo ni, ẹri-ọkàn kì iṣe ti ara rẹ, ṣugbọn ti ẹnikeji rẹ: nitori ẽṣe ti a fi fi ẹri-ọkàn ẹlomiran dá omnira mi lẹjọ? 30 Bi emi bá fi ọpẹ jẹ ẹ, ẽṣe ti a fi nsọ̀rọ mi ni buburu nitori ohun ti emi dupẹ fun? 31 Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun. 32 Ẹ máṣe jẹ́ ohun ikọsẹ, iba ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun: 33 Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.

1 Korinti 11

1 Ẹ mã ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti nṣe afarawe Kristi.

Obinrin Ní láti Bo Orí Ninu Ìsìn

2 Njẹ, ará, mo yìn nyin ti ẹnyin nranti mi ninu ohun gbogbo, ti ẹnyin ti di ẹ̀kọ́ wọnni mu ṣinṣin, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le nyin lọwọ. 3 Ṣugbọn mo fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, Kristi li ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin si li ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi si li Ọlọrun. 4 Olukuluku ọkunrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ ti o bo ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀. 5 Ṣugbọn olukuluku obinrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ li aibò ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀: nitori ọkanna ni pẹlu ẹniti o fári. 6 Nitori bi obinrin kò ba bo ori, ẹ jẹ ki o rẹ́ irun rẹ̀ pẹlu: ṣugbọn bi o bá ṣepe ohun itiju ni fun obinrin lati rẹ́ irun tabi lati fári rẹ̀, jẹ ki o bò ori. 7 Nitori nitõtọ kò yẹ ki ọkunrin ki o bò ori rẹ̀, niwọnbi on ti jẹ aworan ati ogo Ọlọrun: ṣugbọn obinrin ni iṣe ogo ọkunrin. 8 Nitori ọkunrin kò ti ara obinrin wá; ṣugbọn obinrin ni o ti ara ọkunrin wá. 9 Bẹ̃ni a kò dá ọkunrin nitori obinrin; ṣugbọn a da obinrin nitori ọkunrin. 10 Nitori eyi li o fi yẹ fun obinrin lati ni ami aṣẹ li ori rẹ̀, nitori awọn angẹli. 11 Ṣugbọn ọkunrin kò le ṣe laisi obinrin, bẹ̃ni obinrin kò le ṣe laisi ọkunrin ninu Oluwa. 12 Nitori gẹgẹ bi obinrin ti ti ara ọkunrin wá, bẹ̃li ọkunrin tipasẹ obinrin wá pẹlu: ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun li ohun gbogbo ti wá. 13 Ẹ gba a rò lãrin ẹnyin tikaranyin: o ha tọ́ ki obinrin ki o mã gbadura si Ọlọrun laibori? 14 Ani ẹda tikararẹ̀ kò ha kọ́ nyin pe, bi ọkunrin ba ni irun gigun, àbuku ni fun u? 15 Ṣugbọn bi obinrin ba ni irun gigun, ogo li o jẹ fun u: nitoriti a fi irun rẹ̀ fun u fun ibori. 16 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba dabi ẹniti o fẹran iyàn jija, awa kò ni irú aṣa bẹ̃, tabi awọn ijọ Ọlọrun.

Ìwà Tí Kò Dára Nípa Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

17 Ṣugbọn niti aṣẹ ti mo nfun nyin yi, emi kò yìn nyin pe, ẹ npejọ kì iṣe fun rere, ṣugbọn fun buburu. 18 Nitori lọna ikini, mo gbọ́ pe, nigbati ẹnyin pejọ ni ijọ, ìyapa mbẹ lãrin nyin; mo si gbà a gbọ́ li apakan. 19 Nitoripe kò le ṣe ki o má si adamọ pẹlu larin nyin, ki awọn ti o daju larin nyin ba le farahàn. 20 Nitorina nigbati ẹnyin ba pejọ si ibi kanna, kì iṣe lati jẹ Onjẹ Oluwa. 21 Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji. 22 Kinla? ẹnyin kò ni ile nibiti ẹ o mã jẹ, ti ẹ o si mã mu? tabi ẹnyin ngàn ijọ Ọlọrun, ẹnyin si ndojutì awọn ti kò ni? Kili emi o wi fun nyin? emi o ha yìn nyin ninu eyi? emi kò yìn nyin.

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

23 Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara: 24 Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. 25 Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. 26 Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de.

Jíjẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa láìyẹ

27 Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹ akara, ti o si mu ago Oluwa laiyẹ, yio jẹbi ara ati ẹ̀jẹ Oluwa. 28 Ṣugbọn ki enia ki o wadi ara rẹ̀ daju, bẹ̃ni ki o si jẹ ninu akara na, ki o si mu ninu ago na. 29 Nitori ẹnikẹni ti o ba njẹ, ti o ba si nmu laimọ̀ ara Oluwa yatọ, o njẹ o si nmu ẹbi fun ara rẹ̀. 30 Nitori idi eyi li ọ̀pọlọpọ ninu nyin ṣe di alailera ati olokunrun, ti ọ̀pọlọpọ si sùn. 31 Ṣugbọn bi awa ba wadi ara wa, a kì yio da wa lẹjọ. 32 Ṣugbọn nigbati a ba ndá wa lẹjọ, lati ọwọ́ Oluwa li a ti nnà wa, ki a má bã dá wa lẹbi pẹlu aiye. 33 Nitorina, ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba pejọ lati jẹun, ẹ mã duro dè ara nyin. 34 Bi ebi ba npa ẹnikẹni, ki o jẹun ni ile; ki ẹnyin ki o má bã pejọ fun ẹbi. Iyokù li emi ó si tò lẹsẹsẹ nigbati mo ba de.

1 Korinti 12

Àwọn Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

1 NJẸ niti ẹbun ẹmí, ará, emi kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ ope. 2 Ẹnyin mọ̀ pe nigbati ẹnyin jẹ Keferi, a fà nyin lọ sọdọ awọn odi oriṣa, lọnakọna ti a fa nyin. 3 Nitorina mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe, kò si ẹniti nsọ̀rọ nipa Ẹmí Ọlọrun ki o wipe ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, kò si ẹniti o le wipe, Oluwa ni Jesu, bikoṣe nipa Ẹmí Mimọ́. 4 Njẹ onirũru ẹ̀bun li o wà, ṣugbọn Ẹmí kanna ni. 5 Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni. 6 Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn. 7 Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère. 8 Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna; 9 Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna; 10 Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède: 11 Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.

Gbogbo Ìjọ Jẹ́ Ẹ̀yà Ara Kan

12 Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọ̀kan, ti o si li ẹ̀ya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹ̀ya ara ti iṣe pupọ jẹ́ ara kan: bẹ̃ si ni Kristi pẹlu. 13 Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan. 14 Nitoripe ara kì iṣe ẹ̀ya kan, bikoṣe pupọ. 15 Bi ẹsẹ ba wipe, Nitori emi kì iṣe ọwọ́, emi kì iṣe ti ara; eyi kò wipe ki iṣe ti ara. 16 Bi etí ba si wipe, Nitori emi ki iṣe oju, emi kì iṣe ti ara: eyi kò wipe ki iṣe ti ara. 17 Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà? 18 Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u. 19 Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà? 20 Ṣugbọn nisisiyi, nwọn jẹ ẹya pupọ, ṣugbọn ara kan. 21 Oju kò si le wi fun ọwọ́ pe, emi kò ni ifi ọ ṣe: tabi ki ori wi ẹ̀wẹ fun ẹsẹ pe, emi kò ni ifi nyin ṣe. 22 Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù: 23 Ati awọn ẹ̀ya ara wọnni ti awa rò pe nwọn ṣe ailọlá jù, lori wọnyi li awa si nfi ọlá si jù; bẹni ibi aiyẹ wa si ni ẹyẹ lọpọlọpọ jù. 24 Nitoripe awọn ibi ti o li ẹyẹ li ara wa kò fẹ ohun kan: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe ara lọkan, o si fi ọ̀pọlọpọ ọlá fun ibi ti o ṣe alaini: 25 Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn. 26 Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀. 27 Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀. 28 Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède. 29 Gbogbo wọn ni iṣe aposteli bi? gbogbo wọn ni iṣe woli bi? gbogbo wọn ni iṣe olukọni bi? gbogbo wọn ni iṣe iṣẹ iyanu bi? 30 Gbogbo wọn li o li ẹ̀bun imularada bi? gbogbo wọn ni nfi onirũru ède fọ̀ bi? gbogbo wọn ni nṣe itumọ̀ bi? 31 Ṣugbọn ẹ mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti o tobi jù: sibẹ emi o fi ọ̀na kan ti o tayọ rekọja hàn nyin.

1 Korinti 13

1 BI mo tilẹ nfọ oniruru ede ati ti angẹli, ti emi kò si ni ifẹ, emi dabi idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro. 2 Bi mo si ni ẹbun isọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ; bi mo si ni gbogbo igbagbọ́, tobẹ̃ ti mo le ṣí awọn òke nla nipò, ti emi kò si ni ifẹ, emi kò jẹ nkan. 3 Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi. 4 Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, 5 Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; 6 Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; 7 A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo. 8 Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan. 9 Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan. 10 Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin. 11 Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ. 12 Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu. 13 Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.

1 Korinti 14

Ẹ̀bùn Èdè Àjèjì ati Ti Ìsọtẹ́lẹ̀

1 Ẹ mã lepa ifẹ, ki ẹ si mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti iṣe ti Ẹmí, ṣugbọn ki ẹ kuku le mã sọtẹlẹ. 2 Nitori ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀, kò bá enia sọ̀rọ bikoṣe Ọlọrun: nitori kò si ẹniti o gbọ; ṣugbọn nipa ti Ẹmí o nsọ ohun ijinlẹ: 3 Ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ mba awọn enia sọrọ fun imuduro, ati igbiyanju, ati itunu. 4 Ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ nfi ẹsẹ ara rẹ̀ mulẹ; ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ nfi ẹsẹ ijọ mulẹ. 5 Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́. 6 Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́? 7 Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi? 8 Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun? 9 Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu. 10 O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ. 11 Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi. 12 Bẹ̃ si li ẹnyin, bi ẹnyin ti ni itara fun ẹ̀bun ẹmí, ẹ mã ṣe afẹri ati mã pọ si i fun idàgbàsoke ijọ. 13 Nitorina jẹ ki ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ gbadura ki o le mã ṣe itumọ̀. 14 Nitori bi emi ba ngbadura li ède aimọ̀, ẹmí mi ngbadura, ṣugbọn oye mi jẹ alaileso. 15 Njẹ kini rè? Emi o fi ẹmí gbadura, emi o si fi oye gbadura pẹlu: emi o fi ẹmí kọrin, emi o si fi oye kọrin pẹlu. 16 Bi bẹ̃kọ, bi iwọ ba súre nipa, ẹmí, bawo ni ẹniti mbẹ ni ipò òpe yio ṣe ṣe Amin si idupẹ rẹ, nigbati kò mọ ohun ti iwọ wi? 17 Nitori iwọ dupẹ gidigidi nitõtọ, ṣugbọn a kò fi ẹsẹ ẹnikeji rẹ mulẹ. 18 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ti emi nfọ oniruru ede jù gbogbo nyin lọ: 19 Ṣugbọn mo fẹ ki ng kuku fi oye mi sọ ọ̀rọ marun ni ijọ, ki ng le kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu, jù ẹgbãrun ọ̀rọ li ède aimọ̀. 20 Ará, ẹ máṣe jẹ ọmọde ni oye: ṣugbọn ẹ jẹ ọmọde li arankan, ṣugbọn ni oye ki ẹ jẹ agba. 21 A ti kọ ọ ninu ofin pe, Nipa awọn alahọn miran ati elete miran li emi ó fi bá awọn enia yi sọrọ; sibẹ nwọn kì yio gbọ temi, li Oluwa wi. 22 Nitorina awọn ahọn jasi àmi kan, kì iṣe fun awọn ti o gbagbọ́, bikoṣe fun awọn alaigbagbọ́: ṣugbọn isọtẹlẹ kì iṣe fun awọn ti kò gbagbọ́, bikoṣe fun awọn ti o gbagbọ́. 23 Njẹ bi gbogbo ijọ ba pejọ si ibi kan, ti gbogbo nwọn si nfi ède fọ̀, bi awọn ti iṣe alailẹkọ́ ati alaigbagbọ́ ba wọle wá, nwọn kì yio ha wipe ẹnyin nṣe wère? 24 Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀: 25 Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.

Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo Létòlétò

26 Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro. 27 Bi ẹnikan ba fi ède fọ̀, ki o jẹ enia meji, tabi bi o pọ̀ tan, ki o jẹ mẹta, ati eyini li ọkọ̃kan; si jẹ ki ẹnikan gbufọ. 28 Ṣugbọn bi kò ba si ogbufọ, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ninu ijọ; si jẹ ki o mã bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọrọ. 29 Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ. 30 Bi a bá si fi ohunkohun hàn ẹniti o joko nibẹ, jẹ ki ẹni iṣaju dakẹ. 31 Gbogbo nyin le mã sọtẹlẹ li ọkọ̃kan, ki gbogbo nyin le mã kọ ẹkọ ki a le tu gbogbo nyin ni inu. 32 Ẹmí awọn woli a si ma tẹriba fun awọn woli. 33 Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́.

Ipò Obinrin ninu Ìsìn

34 Jẹ ki awọn obinrin nyin dakẹ ninu ijọ: nitori a kò fifun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wà labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi. 35 Bi nwọn ba si fẹ kọ́ ohunkohun, ki nwọn ki o bère lọwọ ọkọ wọn ni ile: nitori ohun itiju ni fun awọn obinrin lati mã sọrọ ninu ijọ. 36 Kini? lọdọ nyin li ọ̀rọ Ọlọrun ti jade ni? tabi ẹnyin nikan li o tọ̀ wá?

Gbolohun Ìparí Nípa Ètò Ìsìn

37 Bi ẹnikẹni ba ro ara rẹ̀ pe on jẹ woli, tabi on jẹ ẹniti o li ẹmí, jẹ ki nkan wọnyi ti mo kọ si nyin ki o ye e daju pe ofin Oluwa ni nwọn. 38 Ṣugbọn bi ẹnikan ba jẹ òpe, ẹ jẹ ki o jẹ òpe. 39 Nitorina, ará, ẹ mã fi itara ṣafẹri lati sọtẹlẹ ki ẹ má si ṣe danilẹkun lati fi ède fọ̀. 40 Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ.

1 Korinti 15

Ajinde Kristi

1 NJẸ, ará, emi nsọ ihinrere na di mimọ̀ fun nyin ti mo ti wãsu fun nyin, eyiti ẹnyin pẹlu ti gbà, ninu eyi ti ẹnyin si duro; 2 Nipaṣe eyiti a fi ngbà nyin là pẹlu, bi ẹnyin ba di ọ̀rọ ti mo ti wãsu fun nyin mú ṣinṣin, bikoṣepe ẹnyin ba gbagbọ́ lasan. 3 Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi; 4 Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi: 5 Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila: 6 Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn. 7 Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli. 8 Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀. 9 Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun. 10 Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi. 11 Nitorina ibã ṣe emi tabi awọn ni, bẹ̃li awa wãsu, bẹ̃li ẹnyin si gbagbọ́.

Ajinde Òkú

12 Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si? 13 Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde: 14 Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu. 15 Pẹlupẹlu a mu wa li ẹlẹri eke fun Ọlọrun; nitoriti awa jẹri Ọlọrun pe o jí Kristi dide: ẹniti on kò jí dide, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde? 16 Nitoripe bi a kò bá ji awọn oku dide, njẹ a kò jí Kristi dide: 17 Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ́ nyin; ẹnyin wà ninu ẹ̀ṣẹ nyin sibẹ. 18 Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé. 19 Bi o ba ṣe pe ni kìki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia. 20 Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. 21 Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. 22 Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi. 23 Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀. 24 Nigbana ni opin yio de, nigbati o ba ti fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba; nigbati o ba ti mu gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọla ati agbara kuro. 25 Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. 26 Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun. 27 Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ. 28 Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo. 29 Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú? 30 Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo? 31 Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́. 32 Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú. 33 Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ. 34 Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin.

Ara Lẹ́yìn Ajinde

35 Ṣugbọn ẹnikan yio wipe, Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si? 36 Iwọ alaimoye, ohun ti iwọ fọnrugbin ki iyè bikoṣepe o ba kú: 37 Ati eyiti iwọ fọnrugbin, ara ti mbọ̀ ki iwọ fọnrugbin, ṣugbọn irugbin lasan ni, ibã ṣe alikama, tabi irú miran. 38 Ṣugbọn Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirẹ̀. 39 Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ. 40 Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ: ṣugbọn ogo ti oke ọrun ọ̀tọ, ati ogo ti aiye ọ̀tọ. 41 Ọtọ li ogo ti õrùn, ọ̀tọ li ogo ti oṣupa, ọ̀tọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo. 42 Gẹgẹ bẹ̃ si li ajinde okú. A gbìn i ni idibajẹ; a si jí i dide li aidibajẹ: 43 A gbìn i li ainiyìn; a si jí i dide li ogo: a gbìn i li ailera, a si jí i dide li agbara: 44 A gbìn i li ara iyara; a si jí i dide li ara ẹmí. Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmí si mbẹ. 45 Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye. 46 Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí. 47 Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni. 48 Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun. 49 Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun. 50 Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹ̀jẹ kò le jogún ijọba Ọlọrun; bẹ̃ni idibajẹ kò le jogún aidibajẹ. 51 Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada, 52 Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà. 53 Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀. 54 Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ̀, ti ara kikú yi ba si ti gbe aikú wọ̀ bẹ̃ tan, nigbana ni ọ̀rọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbé ikú mì ni iṣẹgun. 55 Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà? 56 Oró ikú li ẹ̀ṣẹ; ati agbara ẹ̀ṣẹ li ofin. 57 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi. 58 Nitorina ẹnyin ará mi olufẹ ẹ mã duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mã pọ̀ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ̀ pe iṣẹ nyin kì iṣe asan ninu Oluwa.

1 Korinti 16

Ìtọrẹ Onigbagbọ

1 NJẸ niti idawo fun awọn enia mimọ́, bi mo ti fi aṣẹ fun awọn ijọ Galatia, bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹ ṣe. 2 Li ọjọ ikini ọ̀sẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rẹ̀ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u, ki o máṣe si ikojọ nigbati mo ba de. 3 Ati nigbati mo ba de, ẹnikẹni ti ẹ ba fi iwe nyin yàn, awọn li emi ó rán lati mu ẹ̀bun nyin gòke lọ si Jerusalemu. 4 Bi o ba si yẹ ki emi ki o lọ pẹlu, nwọn ó si ba mi lọ.

Ètò Nípa Ìrìn Àjò

5 Ṣugbọn emi o tọ̀ nyin wá, nigbati emi ba ti kọja lọ larin Makedonia: nitori emi ó kọja larin Makedonia. 6 Boya emi ó si duro, ani, emi a si lo akoko otutu pẹlu nyin, ki ẹnyin ki o le sìn mi li ọ̀na àjo mi, nibikibi ti mo ba nlọ. 7 Nitori emi kò fẹ ri nyin li ọ̀na-ajò nisisiyi; nitori emi nreti ati duro lọdọ nyin nigba diẹ, bi Oluwa ba fẹ. 8 Ṣugbọn emi o duro ni Efesu titi di Pẹntikọsti. 9 Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ. 10 Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe. 11 Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin. 12 Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.

Gbolohun Ìparí

13 Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara. 14 Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin. 15 Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́), 16 Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla. 17 Mo yọ̀ fun wíwa Stefana ati Fortunatu ati Akaiku: nitori eyi ti o kù nipa tinyin nwọn ti fi kún u. 18 Nitoriti nwọn tù ẹmí mi lara ati tinyin: nitorina ẹ mã gbà irú awọn ti o ri bẹ̃. 19 Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn. 20 Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin. 21 Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá. 22 Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata. 23 Õre-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ki o pẹlu nyin. 24 Ifẹ mi wà pẹlu gbogbo nyin ninu Kristi Jesu. Amin.

2 Korinti 1

Ìkíni

1 PAULU Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, si ijọ Ọlọrun ti o wà ni Korinti, pẹlu, gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà ni gbogbo Akaia: 2 Õre-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ọpẹ́ lẹ́yìn ìjìyà

3 Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo; 4 Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu. 5 Nitoripe bi ìya Kristi ti di pipọ ninu wa, gẹgẹ bẹ̃ni itunu wa di pipọ pẹlu nipa Kristi. 6 Ṣugbọn bi a ba si npọ́n wa loju ni, o jasi bi itunu ati igbala nyin, ti nṣiṣẹ ni ifàiyarán awọn iya kannã ti awa pẹlu njẹ: tabi bi a ba ntù wa ninu, o jasi fun itunu ati igbala nyin. 7 Ati ireti wa nipa tiyin duro ṣinṣin, awa si mọ̀ pe, bi ẹnyin ti jẹ alabapin ninu ìya, bẹ̃li ẹnyin jẹ ninu itunu na pẹlu. 8 Ará, awa kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li aimọ̀ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọ́n wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹ̃ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ́: 9 Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide: 10 Ẹniti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹ̃, ti o si ngbà wa: ẹniti awa gbẹkẹ wa le pe yio si mã gbà wa sibẹsibẹ; 11 Ẹnyin pẹlu nfi adura nyin ṣe iranlọwọ fun wa, pe nitori ẹ̀bun ti a fifun wa lati ọwọ ọ̀pọlọpọ enia, ki ọ̀pọlọpọ ki o le mã dupẹ nitori wa.

Ìdí Tí Paulu Ṣe Yí Ètò Ìrìn Àjò Rẹ̀ Pada

12 Nitori eyi ni iṣogo wa, ẹ̀rí-ọkàn wa, pe, ni iwa-mimọ́ ati ododo Ọlọrun, kì iṣe nipa ọgbọ́n ara, bikoṣe nipa ore-ọfẹ Ọlọrun, li awa nhuwa li aiye, ati si nyin li ọ̀pọlọpọ. 13 Nitoripe awa kò kọwe ohun miran si nyin jù eyi ti ẹnyin kà lọ, tabi ti ẹnyin ti gbà pẹlu: mo si gbẹkẹle pe ẹnyin ó gba a titi de opin; 14 Gẹgẹ bi ẹnyin si ti jẹwọ wa pẹlu li apakan pe, awa ni iṣogo nyin, gẹgẹ bi ẹnyin pẹlu ti jẹ iṣogo wa li ọjọ Jesu Oluwa. 15 Ati ninu igbẹkẹle yi ni mo ti ngbèro ati tọ̀ nyin wá niṣãjú, ki ẹnyin ki o le ni ayọ nigbakeji; 16 Ati lati kọja lọdọ nyin lọ si Makedonia, ati lati tún wá sọdọ nyin lati Makedonia, ati lati mu mi lati ọdọ nyin lọ si Judea. 17 Nitorina nigbati emi ngbèro bẹ̃, emi ha ṣiyemeji bi? tabi ohun wọnni ti mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹgẹ bi ti ara bi, pe ki o jẹ bẹ̃ni bẹ̃ni, ati bẹ̃kọ, bẹ̃kọ lọdọ mi? 18 Ṣugbọn bi Ọlọrun ti jẹ olõtọ, ọ̀rọ wa fun nyin kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ. 19 Nitoripe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, ẹniti a ti wasu rẹ̀ larin nyin nipasẹ wa, ani nipasẹ emi ati Silfanu ati Timotiu, kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ, ṣugbọn ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni. 20 Nitoripe bi o ti wu ki ileri Ọlọrun pọ̀ to, ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni: ati ninu rẹ̀ pẹlu ni Amin, si ogo Ọlọrun nipasẹ wa. 21 Njẹ nisisiyi, ẹniti o fi ẹsẹ wa mulẹ pẹlu nyin ninu Kristi, ti o si fi àmi oróro yàn wa, ni Ọlọrun; 22 Ẹniti o si ti fi èdidi di wa pẹlu, ti o si ti fi akọso eso Ẹmí si wa li ọkàn. 23 Mo si pè Ọlọrun ṣe ẹlẹri li ọkàn mi pe, nitori lati dá nyin si li emi kò ṣe ti wá si Korinti. 24 Kì iṣe nitoriti awa tẹ́ gàbá lori igbagbọ́ nyin, ṣugbọn awa jẹ́ oluranlọwọ ayọ̀ nyin: nitori ẹnyin duro nipa igbagbọ́.

2 Korinti 2

1 ṢUGBỌN mo ti pinnu eyi ninu emi tikarami pe, emi kì yio tun fi ibinujẹ tọ̀ nyin wá. 2 Nitoripe bi emi ba mu inu nyin bajẹ, njẹ tali ẹniti o si nmu inu mi dùn, bikoṣe ẹniti mo ti bà ninu jẹ? 3 Emi si kọwe nitori eyi kanna si nyin pe, nigbati mo ba si de, ki emi ki o máṣe ni ibinujẹ lọdọ wọn, nitori awọn ti emi iba mã yọ̀: nitoriti mo ni igbẹkẹle ninu gbogbo nyin, nitori ayọ̀ mi li ayọ̀ fun gbogbo nyin. 4 Nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ wahalà ati arodun ọkan mi ni mo ti fi ọ̀pọlọpọ omije kọwe si nyin; kì iṣe nitori ki a le bà nyin ninu jẹ, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ ifẹ ti mo ni si nyin lọpọlọpọ rekọja.

Ẹ Dárí Ji Ẹni Tí Ó Ṣe Àìdára

5 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba ti mu ibinujẹ wá, on kò bà mi ni inu jẹ, bikoṣe niwọn diẹ: ki emi ki o máṣe di ẹru l'ẹ̀ru gbogbo nyin. 6 Ìya yi ti ọpọlọpọ ti fi jẹ iru enia bẹ̃, o to fun u. 7 Kaka bẹ ẹ, ẹnyin iba kuku darijì i, ki ẹ si tù u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má bã bò iru enia bẹ̃ mọlẹ. 8 Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ fi ifẹ nyin han daju si oluwarẹ̀. 9 Nitori eyi na pẹlu ni mo ti kọwe, ki emi ki o le mọ̀ ẹri nyin, bi ẹnyin ba ṣe eletí ọmọ li ohun gbogbo. 10 Ṣugbọn ẹniti ẹnyin ba fi ohunkohun jì fun, emi fi jì pẹlu: nitori ohun ti emi pẹlu ba ti fi jì, bi mo ba ti fi ohunkohun jì, nitori tinyin ni mo ti fi ji niwaju Kristi. 11 Ki Satani má bã rẹ́ wa jẹ: nitori awa kò ṣe alaimọ̀ arekereke rẹ̀.

Ọkàn Paulu Balẹ̀ Lẹ́yìn Àníyàn

12 Ṣugbọn nigbati mo de Troa lati wãsu ihinrere Kristi, ti ilẹkun si ṣí silẹ fun mi lati ọdọ Oluwa wá, 13 Emi kò ni alafia li ọkàn mi, nitoriti emi ko ri Titu arakunrin mi: ṣugbọn nigbati mo ti dagbere fun wọn, mo rekọja lọ si Makedonia. 14 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ̀ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi, ti o si nfi õrùn ìmọ rẹ̀ hàn nipa wa nibigbogbo. 15 Nitori õrun didùn Kristi li awa jẹ fun Ọlọrun, ninu awọn ti a ngbalà, ati ninu awọn ti o nṣegbé: 16 Fun awọn kan, awa jẹ õrun ikú si ikú, ati fun awọn miran õrun iyè. Tali o ha si to fun nkan wọnyi? 17 Nitori awa kò dabi awọn ọ̀pọlọpọ, ti mba ọ̀rọ Ọlọrun jẹ́: ṣugbọn bi nipa otitọ inu, ṣugbọn bi lati ọdọ Ọlọrun wá, niwaju Ọlọrun li awa nsọ̀rọ ninu Kristi.

2 Korinti 3

Òjíṣẹ́ Majẹmu Titun

1 AWA ha tún bẹ̀rẹ lati mã yìn ara wa bi? tabi awa ha nfẹ iwe iyìn sọdọ nyin, tabi lati ọdọ nyin bi awọn ẹlomiran? 2 Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà: 3 Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran. 4 Irú igbẹkẹle yi li awa si ni nipa Kristi sọdọ Ọlọrun: 5 Kì iṣe pe awa to fun ara wa lati ṣirò ohunkohun bi ẹnipe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni tito wa; 6 Ẹniti o mu wa tó bi iranṣẹ majẹmu titun; kì iṣe ti iwe, bikoṣe ti ẹmí: nitori iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmí a mã sọni di ãye. 7 Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ), 8 Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù? 9 Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo. 10 Nitori eyi ti a tilẹ ṣe logo, kò li ogo mọ́ nitori eyi, nipasẹ ogo ti o tayọ. 11 Nitoripe bi eyi ti nkọja lọ ba li ogo, melomelo li eyi ti o duro li ogo. 12 Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ. 13 Kì si iṣe bi Mose, ẹniti o fi iboju bo oju rẹ̀, ki awọn ọmọ Israeli má ba le tẹjumọ wo opin eyi ti nkọja lọ. 14 Ṣugbọn oju-inu wọn fọ́: nitoripe titi fi di oni oloni ní kika majẹmu lailai, iboju na wà laiká soke; iboju ti a ti mu kuro ninu Kristi. 15 Ṣugbọn titi di oni oloni, nigbakugba ti a ba nkà Mose, iboju na mbẹ li ọkàn wọn. 16 Ṣugbọn nigbati on o ba yipada si Oluwa, a o mu iboju na kuro. 17 Njẹ Oluwa li Ẹmí na: nibiti Ẹmí Oluwa ba si wà, nibẹ̀ li omnira gbé wà. 18 Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.

2 Korinti 4

Ìṣúra ti Ẹ̀mí Ninu ìkòkò Amọ̀

1 NITORINA bi awa ti ni iṣẹ-iranṣẹ yi, gẹgẹ bi a ti ri ãnu gbà, ãrẹ̀ kò mu wa; 2 Ṣugbọn awa ti kọ̀ gbogbo ohun ìkọkọ ti o ni itiju silẹ, awa kò rìn li ẹ̀tan, bẹ̃li awa kò fi ọwọ́ ẹ̀tan mu ọ̀rọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa fifi otitọ hàn, awa nfi ara wa le ẹri-ọkàn olukuluku enia lọwọ niwaju Ọlọrun. 3 Ṣugbọn bi ihinrere wa ba si farasin, o farasin fun awọn ti o nù: 4 Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn. 5 Nitori awa kò wãsu awa tikarawa, bikoṣe Kristi Jesu Oluwa; awa tikarawa si jẹ ẹrú nyin nitori Jesu. 6 Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi. 7 Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá. 8 A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù. 9 A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run; 10 Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa. 11 Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu. 12 Bẹ̃ni ikú nṣiṣẹ ninu wa, ṣugbọn ìye ninu nyin. 13 Awa li ẹmí igbagbọ́ kanna, gẹgẹ bi a ti kọ́ ọ pe, emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: awa pẹlu gbagbọ́, nitorina li awa si ṣe nsọ; 14 Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin. 15 Nitoripe tinyin li ohun gbogbo, ki ọpọ̀ ore-ọfẹ nipa awọn pipọ le mu ki ọpẹ di pipọ fun ogo Ọlọrun.

Ìgbé-Ayé Nípa Igbagbọ

16 Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́. 17 Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa. 18 Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.

2 Korinti 5

1 NITORI awa mọ̀ pe, bi ile agọ́ wa ti aiye bá wó, awa ni ile kan lati ọdọ Ọlọrun, ile ti a kò fi ọwọ́ kọ́, ti aiyeraiye ninu awọn ọrun. 2 Nitori nitõtọ awa nkerora ninu eyi, awa si nfẹ gidigidi lati fi ile wa lati ọrun wá wọ̀ wa: 3 Bi o ba ṣepe a ti wọ̀ wa li aṣọ, a kì yio bá wa ni ìhoho. 4 Nitori awa ti mbẹ ninu agọ́ yi nkerora nitõtọ, ẹrù npa wa: kì iṣe nitori ti awa nfẹ ijẹ alaiwọ̀ṣọ, ṣugbọn ki a le wọ̀ wa li aṣọ, ki iyè ki o le gbé ara kiku mì. 5 Njẹ ẹniti o ṣe wa fun nkan yi ni Ọlọrun, ẹniti o si ti fi akọso Ẹmí fun wa pẹlu. 6 Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa: 7 (Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:) 8 Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa. 9 Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀. 10 Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.

Iṣẹ́ Ìlàjà

11 Nitorina bi awa ti mọ̀ ẹ̀ru Oluwa, awa nyi enia li ọkàn pada; ṣugbọn a nfi wa hàn fun Ọlọrun; mo si gbagbọ́ pe, a si fi wa hàn li ọkàn nyin pẹlu. 12 Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn. 13 Nitorina bi ori wa ba bajẹ, fun Ọlọrun ni: tabi bi iye wa ba walẹ̀, fun nyin ni. 14 Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú: 15 O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde. 16 Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́. 17 Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun. 18 Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa; 19 Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ. 20 Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja. 21 Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.

2 Korinti 6

1 NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan. 2 (Nitori o wipe, emi ti gbohùn rẹ li akokò itẹwọgbà, ati li ọjọ igbala ni mo si ti ràn ọ lọwọ: kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.) 3 A kò si ṣe ohun ikọsẹ li ohunkohun, ki iṣẹ-iranṣẹ ki o máṣe di isọrọ buburu si. 4 Ṣugbọn li ohun gbogbo awa nfi ara wa han bi awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu ọ̀pọlọpọ sũru, ninu ipọnju, ninu aini, ninu wahalà, 5 Nipa ìnà, ninu tubu, nipa ìrúkerudo, nipa ìṣẹ́, ninu iṣọra, ninu igbawẹ; 6 Nipa ìwa mimọ́, nipa ìmọ, nipa ipamọra, nipa iṣeun, nipa Ẹmi Mimọ́, nipa ifẹ aiṣẹtan, 7 Nipa ọ̀rọ otitọ, nipa agbara Ọlọrun, nipa ihamọra ododo li apa ọtún ati li apa òsi, 8 Nipa ọlá ati ẹ̀gan, nipa ìhin buburu ati ìhin rere: bi ẹlẹtan, ṣugbọn a jasi olõtọ; 9 Bi ẹniti a kò mọ̀, ṣugbọn a mọ̀ wa dajudaju; bi ẹniti nkú lọ, si kiyesi i, awa wà lãye; bi ẹniti a ńnà, a kò si pa wa; 10 Bi ẹniti o kún fun ibinujẹ, ṣugbọn awa nyọ̀ nigbagbogbo; bi talakà, ṣugbọn awa nsọ ọ̀pọlọpọ di ọlọrọ̀; bi ẹniti kò ni nkan, ṣugbọn awa ni ohun gbogbo. 11 Ẹnyin ara Korinti, a ti bá nyin sọ otitọ ọ̀rọ, ọkàn wa ṣipayá sí nyin. 12 A kò ni nyin lara nitori wa, ṣugbọn a ńni nyin lara nitori ifẹ-ọkàn ẹnyin tikaranyin. 13 Njẹ fun ẹsan iru kanna (emi nsọ bi ẹnipe fun awọn ọmọ mi,) ki ẹnyin di kikún pẹlu.

Ilé Ọlọrun Alààyè

14 Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ́: nitori ìdapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ si ni pẹlu òkunkun? 15 Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ? 16 Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. 17 Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin. 18 Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.

2 Korinti 7

1 NITORINA, ẹnyin olufẹ, bi a ti ni ileri wọnyi, ẹ jẹ ki a wẹ̀ ara wa mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin ti ara ati ti ẹmí, ki a mã sọ ìwa mimọ́ di pipé ni ìbẹru Ọlọrun.

Inú Paulu Dùn Nígbà Tí Ìjọ Ronupiwada

2 Ẹ gbà wa tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹni, a kò bà ẹnikẹni jẹ, a kò rẹ́ ẹnikẹni jẹ. 3 Emi kò sọ eyi lati da nyin lẹbi: nitori mo ti wi ṣãjú pe, ẹnyin wà li ọkàn wa ki a le jumọ kú, ati ki a le jumọ wà lãye. 4 Mo ni igboiya nla lati ba nyin sọ̀rọ, iṣogo mi lori nyin pọ̀, mo kun fun itunu, mo si nyọ̀ rekọja ninu gbogbo ipọnju wa. 5 Nitoripe nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ìja mbẹ lode, ẹ̀ru mbẹ ninu. 6 Ṣugbọn ẹniti ntù awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa didé Titu; 7 Kì si iṣe nipa didé rẹ̀ nikan, ṣugbọn nipa itunu na pẹlu ti ẹ ti tù u ninu, nigbati o rohin fun wa ifẹ gbigbona nyin, ibanujẹ nyin, ati itara nyin fun mi; bẹni mo si tubọ yọ̀. 8 Nitoripe bi mo tilẹ fi iwe mu inu nyin bajẹ, emi kò kãbámọ̀, bi mo tilẹ ti kabamọ rí: nitoriti mo woye pe iwe nì mu nyin banujẹ, bi o tilẹ jẹ pe fun igba diẹ. 9 Emi yọ̀ nisisiyi, kì iṣe nitoriti a mu inu nyin bajẹ, ṣugbọn nitoriti a mu inu nyin bajẹ si ironupiwada: nitoriti a mu inu nyin bajẹ bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, ki ẹnyin ki o maṣe tipasẹ wa pàdanù li ohunkohun. 10 Nitoripe ibanujẹ ẹni ìwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti kì mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú. 11 Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, iṣọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti tó, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na. 12 Nitorina, bi mo tilẹ ti kọwe si nyin, emi kò kọ ọ nitori ẹniti o ṣe ohun buburu na, tabi nitori ẹniti a fi ohun buburu na ṣe, ṣugbọn ki aniyan nyin nitori wa le farahan niwaju Ọlọrun. 13 Nitorina a ti fi itunu nyin tù wa ninu; ati ni itunu wa a yọ̀ gidigidi nitori ayọ̀ Titu, nitori lati ọdọ gbogbo nyin li a ti tu ẹmi rẹ̀ lara. 14 Bi mo tilẹ ti leri ohunkohun fun u nitori nyin, a kò dojuti mi; ṣugbọn gẹgẹ bi awa ti sọ ohun gbogbo fun nyin li otitọ, gẹgẹ bẹ̃li ori ti a lé niwaju Titu si jasi otitọ. 15 Iyọ́nu rẹ̀ si di pupọ̀ gidigidi si nyin, bi on ti nranti igbọran gbogbo nyin, bi ẹ ti fi ibẹru ati iwarìri tẹwọgbà a. 16 Mo yọ̀ nitoripe li ohun gbogbo mo ni igbẹkẹle ninu nyin.

2 Korinti 8

Àwọn Onigbagbọ Ará Masedonia Lawọ́

1 PẸLUPẸLU, ará, awa nsọ fun nyin niti ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun awọn ijọ Makedonia; 2 Bi o ti jẹ pe ninu ọpọ idanwò ipọnju, ọ̀pọlọpọ ayọ̀ wọn ati ibu aini wọn di pipọ si ọrọ̀ ilawọ wọn, 3 Nitori mo jẹri pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, nwọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn, 4 Nwọn nfi ẹ̀bẹ pipọ rọ̀ wa niti ẹbun ọfẹ yi, ati ti idapọ ninu iṣẹ-iranṣẹ fun awọn enia mimọ́: 5 Ati eyi, ki iṣe bi awa ti rò rí, ṣugbọn nwọn tètekọ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun; 6 Tobẹ̃ ti awa fi gba Titu niyanju pe, bi o ti bẹ̀rẹ na, bẹ̃ni ki o si pari ẹbun ọfẹ yi ninu nyin pẹlu. 7 Ṣugbọn bi ẹnyin ti pọ̀ li ohun gbogbo, ni igbagbọ́, ati ọ̀rọ, ati ìmọ, ati ninu igbiyanjú gbogbo, ati ni ifẹ nyin si wa, ẹ kiyesi ki ẹnyin ki o pọ̀ ninu ẹbun ọfẹ yi pẹlu. 8 Kì iṣe nipa aṣẹ ni mo fi nsọ, ṣugbọn ki a le ri idi otitọ ifẹ nyin pẹlu, nipa igbiyanjú awọn ẹlomiran. 9 Nitori ẹnyin mọ̀ ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi on ti jẹ ọlọrọ̀ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ̀ nipa aini rẹ̀. 10 Ati ninu eyi ni mo fi imọran mi fun nyin: nitori eyi ṣanfani fun nyin, ẹnyin ti o kọ́ bẹrẹ niwọn ọdún ti o kọja, kì iṣe lati ṣe nikan, ṣugbọn lati fẹ́ pẹlu. 11 Njẹ nisisiyi ẹ pari ṣiṣe na pẹlu; bi imura-tẹlẹ ati ṣe ti wa, bẹni ki ipari si wa lati inu agbara nyin: 12 Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni. 13 Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin, 14 Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà: 15 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.

Titu ati Àwọn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀

16 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti o fi itara aniyan kanna yi si ọkàn Titu fun nyin. 17 Nitori on gbà ọ̀rọ iyanju nitõtọ; ṣugbọn bi o ti ni itara pipọ, on tikararẹ̀ tọ̀ nyin wá fun ara rẹ̀. 18 Awa ti rán arakunrin na pẹlu rẹ̀, iyìn ẹniti o wà ninu ihinrere yiká gbogbo ijọ. 19 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn ẹniti a ti yàn pẹlu lati ọdọ ijọ wá lati mã bá wa rìn kiri ninu ọran ore-ọfẹ yi, ti awa nṣe iranṣẹ rẹ̀ fun ogo Oluwa, ati imura-tẹlẹ wa. 20 Awa nyẹra fun eyi, ki ẹnikẹni má bã ri wi si wa nitori ọ̀pọ yi ti awa pin. 21 Awa ngbero ohun rere, kì iṣe niwaju Oluwa nikan, ṣugbọn niwaju enia pẹlu. 22 Awa si ti rán arakunrin wa pẹlu wọn, ẹniti awa ri daju nigba pipọ pe o ni itara ninu ohun pipọ, ṣugbọn nisisiyi ni itara rẹ̀ tubọ pọ si i nipa igbẹkẹle nla ti o ni si nyin. 23 Bi ẹnikẹni ba mbère ẹniti Titu iṣe, ẹlẹgbẹ ati olubaṣiṣẹ mi ni nitori nyin: tabi awọn arakunrin wa li ẹnikẹni mbère ni, iranṣẹ ijọ ni nwọn iṣe, ati ogo Kristi. 24 Nitorina ẹ fi ẹri ifẹ nyin hàn wọn niwaju ijọ, ati iṣogo wa nitori nyin.

2 Korinti 9

Ọrẹ fún Àwọn Onigbagbọ

1 NITORI nipa ti ipinfunni fun awọn enia mimọ́, kò ni pe mo nkọwe si nyin ju bẹ̃ lọ. 2 Nitori mo mọ̀ imura-tẹlẹ nyin, eyiti mo fi yangàn fun awọn ara Makedonia nitori nyin, pe, Akaia ti mura tan niwọn ọdún kan ti o kọja; itara nyin si ti rú ọ̀pọlọpọ soke. 3 Ṣugbọn mo ti rán awọn arakunrin, ki iṣogo wa nitori nyin ki o máṣe jasi asan niti ọ̀ran yi; pe gẹgẹ bi mo ti wi, ki ẹnyin ki o le mura tẹlẹ: 4 Bi awọn ninu ará Makedonia ba bá mi wá, ti nwọn si bá nyin li aimura tẹlẹ, ki oju ki o máṣe tì wa (laiwipe ẹnyin,) niti igbẹkẹle yi. 5 Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro. 6 Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká. 7 Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ. 8 Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo: 9 (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai. 10 Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.) 11 Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa. 12 Nitori iṣẹ-iranṣẹ ìsin yi kò fi kun iwọn aini awọn enia mimọ́ nikan, ṣugbọn o tubọ pọ si i nipa ọ̀pọlọpọ ọpẹ́ si Ọlọrun, 13 Lẹhin ti nwọn fi iṣẹ-isin yi dan nyin wo, nwọn yin Ọlọrun li ogo fun itẹriba ijẹwọ́ nyin si ihinrere Kristi, ati fun ilàwọ ìdawó nyin fun wọn ati fun gbogbo enia; 14 Nigbati awọn tikarawọn pẹlu ẹ̀bẹ nitori nyin nṣafẹri nyin nitori ọpọ ore-ọfẹ Ọlọrun ti mbẹ ninu nyin. 15 Ọpẹ́ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ ẹ̀bun rẹ̀.

2 Korinti 10

Paulu Gbèjà Ara Rẹ̀

1 ṢUGBỌN emi Paulu tikarami fi inu tutù ati ìwa pẹlẹ Kristi bẹ̀ nyin, emi ẹni irẹlẹ loju nyin nigbati mo wà larin nyin, ṣugbọn nigbati emi kò si, mo di ẹni igboiya si nyin. 2 Ṣugbọn emi bẹ̀ nyin pe ki o máṣe nigbati mo wà larin nyin ni mo fi igboiya han pẹlu igbẹkẹle ti mo rò pe mo ni igboiya si awọn kan, ti nrò wa si bi ẹniti nrin nipa ti ara. 3 Nitoripe bi awa tilẹ nrìn ni ti ara, ṣugbọn awa kò jagun nipa ti ara: 4 (Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;) 5 Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi; 6 Awa si ti mura tan lati gbẹsan gbogbo aigbọran, nigbati igbọran nyin ba pé. 7 Ẹnyin si nwò nkan gẹgẹ bi nwọn ti fi ara hàn lode. Bi ẹnikẹni ba gbẹkẹle ara rẹ̀ pe, ti Kristi li on iṣe, ẹ jẹ ki on ki o si tún rò eyi ninu ara rẹ̀ pe, bi on ti jẹ́ ti Kristi, gẹgẹ bẹ̃li awa pẹlu si jẹ́ ti Kristi. 8 Nitori bi mo tilẹ nṣogo aṣerekọja nitori aṣẹ wa, ti Oluwa ti fifun wa fun idagbasoke nyin ki iṣe fun ìbiṣubu nyin, oju ki yio tì mi; 9 Ki o máṣe dabi ẹnipe emi o fi iwe-kikọ dẹruba nyin. 10 Nitori nwọn wipe, iwe rẹ̀ wuwo, nwọn si lagbara; ṣugbọn ìrísi rẹ̀ jẹ alailera, ọ̀rọ rẹ̀ kò nilari. 11 Ki irú enia bẹ̃ ki o ro bayi pe, irú ẹniti awa iṣe li ọ̀rọ nipa iwe-kikọ nigbati awa kò si, irú bẹ̃li awa o si jẹ ni iṣe pẹlu nigbati awa ba wà. 12 Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ́, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti ńyìn ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn. 13 Ṣugbọn awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, ṣugbọn nipa ãlà ti Ọlọrun ti pín fun wa, ani ãlà kan lati de ọdọ nyin. 14 Nitori awa kò nawọ́ wa rekọja rara, bi ẹnipe awa kò de ọdọ nyin: nitori awa tilẹ de ọdọ nyin pẹlu ninu ihinrere Kristi. 15 Awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, eyini ni lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ nyin ti ndagba si i, gẹgẹ bi àla wa awa o di gbigbega lọdọ nyin si i lọpọlọpọ, 16 Ki a ba le wasu ihinrere ani ni ẹkùn ti mbẹ niwaju nyin, ki a má si ṣogo ninu ãlà ẹlomiran nipa ohun ti o wà li arọwọto. 17 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa. 18 Nitoripe kì iṣe ẹniti nyìn ara rẹ̀ li o yanju, bikoṣe ẹniti Oluwa yìn.

2 Korinti 11

Paulu ati Àwọn Aposteli Èké

1 ẸNYIN iba gbà mi diẹ ninu wère mi: ati nitotọ, ẹ gbà mi. 2 Nitoripe emi njowú lori nyin niti owú ẹni ìwa-bi-Ọlọrun: nitoriti mo ti fi nyin fun ọkọ kan, ki emi ki o le mu nyin wá bi wundia ti o mọ́ sọdọ Kristi. 3 Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi. 4 Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a. 5 Nitori mo ṣiro rẹ pe emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na. 6 Ṣugbọn bi mo tilẹ jẹ òpe li ọ̀rọ, ki iṣe ni ìmọ; ṣugbọn awa ti fihan dajudaju fun nyin lãrin gbogbo enia. 7 Tabi ẹ̀ṣẹ ni mo dá ti emi nrẹ̀ ara mi silẹ ki a le gbé nyin ga, nitoriti mo ti wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin lọfẹ? 8 Emi ja ijọ miran li ole, mo ngbà owo ki emi ki o le sìn nyin. 9 Nigbati mo si wà pẹlu nyin, ti mo si ṣe alaini, emi kò jẹ́ ẹrù fun ẹnikẹni: nitoriti ohun ti mo ṣe alaini awọn ara ti o ti Makedonia wá fi kún u; ati ninu ohun gbogbo mo ti pa ara mi mọ́ ki emi maṣe jẹ ẹrù fun nyin, bẹ̃li emi ó si mã pa ara mi mọ́. 10 Bi otitọ Kristi ti mbẹ ninu mi, kò sí ẹniti o le da mi lẹkun iṣogo yi ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11 Nitori kini? nitori emi kò fẹran nyin ni bi? Ọlọrun mọ̀. 12 Ṣugbọn ohun ti mo nṣe li emi ó si mã ṣe, ki emi ki o le mu igberaga kuro lọwọ awọn ti gberaga pe ninu ohun ti nwọn nṣogo, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa. 13 Nitori irú awọn enia bẹ̃ li awọn eke Aposteli, awọn ẹniti nṣiṣẹ ẹ̀tan, ti npa ara wọn dà di Aposteli Kristi. 14 Kì si iṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ̀ npa ara rẹ̀ dà di angẹli imọlẹ. 15 Nitorina kì iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

Ìjìyà Paulu Ninu Iṣẹ́ Rẹ̀ Bí Aposteli

16 Mo si tún wipe, Ki ẹnikẹni ki o máṣe rò pe aṣiwère ni mi; ṣugbọn bi bẹ̃ ba ni, ẹ gbà mi bi aṣiwere, ki emi ki o le gbé ara mi ga diẹ. 17 Ohun ti emi nsọ, emi kò sọ ọ nipa ti Oluwa, ṣugbọn bi aṣiwèrè ninu igbẹkẹle iṣogo yi. 18 Ọpọlọpọ li o sa nṣogo nipa ti ara, emi ó ṣogo pẹlu. 19 Nitori ẹnyin fi inu didùn gbà awọn aṣiwère, nigbati ẹnyin tikaranyin jẹ ọlọ́gbọn. 20 Nitori ẹnyin farada a bi ẹnikan ba sọ nyin di ondè, bi ẹnikan ba jẹ nyin run, bi ẹnikan ba gbà lọwọ nyin, bi ẹnikan ba gbé ara rẹ̀ ga, bi ẹnikan ba gbá nyin loju. 21 Emi nwi lọna ẹ̀gan, bi ẹnipe awa jẹ alailera. Ṣugbọn ninu ohunkohun ti ẹnikan ni igboiya (emi nsọrọ were), emi ni igboiya pẹlu. 22 Heberu ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Israeli ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Irú ọmọ Abrahamu ni nwọn bi? bẹ̃li emi. 23 Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ. 24 Nigba marun ni mo gbà paṣan ogoji dín kan lọwọ awọn Ju. 25 Nigba mẹta li a fi ọgọ lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li okuta, ẹ̃mẹta li ọkọ̀ rì mi, ọsán kan ati oru kan ni mo wà ninu ibú. 26 Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin; 27 Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho. 28 Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ. 29 Tani iṣe alailera, ti emi kò ṣe alailera? tabi tali a mu kọsẹ̀, ti ara mi kò gbina? 30 Bi emi kò le ṣaima ṣogo, emi o kuku mã ṣogo nipa awọn nkan ti iṣe ti ailera mi. 31 Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, ẹniti iṣe olubukún julọ lailai, mọ̀ pe emi kò ṣeke. 32 Ni Damasku, bãlẹ ti o wà labẹ ọba Areta fi ẹgbẹ ogun ká ilu awọn ara Damasku mọ́, o nfẹ mi lati mu: 33 Ati loju ferese ninu agbọ̀n li a si ti sọ̀ mi kalẹ lẹhin odi, ti mo si bọ́ lọwọ rẹ̀.

2 Korinti 12

Àwọn Ìran Tí Paulu Rí

1 EMI ko le ṣe aiṣogo bi kò tilẹ ṣe anfani. Nitori emi ó wá si iran ati iṣipaya Oluwa. 2 Emi mọ̀ ọkunrin kan ninu Kristi ni ọdún mẹrinla sẹhin, (yala ninu ara ni, emi kò mọ̀; tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀; Ọlọrun ni o mọ): a gbé irú enia bẹ̃ lọ si ọ̀run kẹta. 3 Emi si ti mọ̀ irú ọkunrin bẹ̃, (yala li ara ni, tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀: Ọlọrun mọ̀) 4 Bi a ti gbé e lọ soke si Paradise, ti o si gbọ́ ọ̀rọ ti a kò le sọ, ti kò tọ́ fun enia lati mã sọ. 5 Nipa irú ẹni bẹ̃ li emi ó ma ṣogo: ṣugbọn nipa ti emi tikarami emi kì yio ṣogo, bikoṣe ninu ailera mi. 6 Nitoripe bi emi tilẹ nfẹ mã ṣogo, emi kì yio jẹ aṣiwère; nitoripe emi ó sọ otitọ: ṣugbọn mo kọ̀, ki ẹnikẹni ki o má bã fi mi pè jù ohun ti o ri ti emi jẹ lọ, tabi ju eyiti o gbọ lẹnu mi. 7 Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja. 8 Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi. 9 On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi. 10 Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara.

Paulu Ní Àníyàn fún Ìjọ Kọrinti

11 Mo di wère nipa ṣiṣogo; ẹnyin li o mu mi ṣe e: nitoriti o tọ́ ti ẹ ba yìn mi: nitoriti emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na, bi emi kò tilẹ jamọ nkankan. 12 Nitõtọ a ti ṣe iṣẹ àmi Aposteli larin nyin ninu sũru gbogbo, ninu iṣẹ àmi, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara. 13 Nitori ninu kili ohun ti ẹnyin rẹ̀hin si ijọ miran, bikoṣe niti pe emi tikarami ko jẹ oniyọnu fun nyin? ẹ dari aṣiṣe yi ji mi. 14 Kiyesi i, igba kẹta yi ni mo mura tan lati tọ̀ nyin wá; emi kì yio si jẹ oniyọnu fun nyin: nitoriti emi kò wá nkan nyin, bikoṣe ẹnyin tikaranyin: nitoriti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati mã tò iṣura jọ fun awọn õbi wọn, bikoṣe awọn õbi fun awọn ọmọ wọn. 15 Emi ó si fi ayọ̀ náwo, emi ó si ná ara mi fun ọkàn nyin nitõtọ; bi mo tilẹ fẹ nyin lọpọlọpọ, diẹ li a ha fẹran mi? 16 Ṣugbọn o dara bẹ̃, ti emi kò dẹruba nyin: ṣugbọn bi ọlọgbọn, emi nfi ẹ̀rọ mu nyin. 17 Emi ha rẹ́ nyin jẹ nipa ẹnikẹni ninu awọn ti mo rán si nyin bi? 18 Mo bẹ̀ Titu, mo si rán arakunrin kan pẹlu rẹ̀; Titu ha rẹ́ nyin jẹ bi? nipa ẹmí kanna kọ́ awa rìn bi? ọ̀na kanna kọ́ awa tọ̀ bi? 19 Ẹnyin ha rò pe ni gbogbo akoko yi àwa nṣe àwíjàre niwaju nyin? awa nsọ̀rọ niwaju Ọlọrun ninu Kristi: ṣugbọn awa nṣe ohun gbogbo, olufẹ ọwọn, lati mu nyin duro. 20 Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà: 21 Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.

2 Korinti 13

Ìkìlọ̀ Ìgbẹ̀yìn

1 EYI li o di igba kẹta ti emi ntọ̀ nyin wá. Li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta li a o fi idi ọ̀rọ gbogbo mulẹ. 2 Mo ti sọ fun nyin ṣaju, mo si nsọ fun nyin tẹlẹ, bi ẹnipe mo wà pẹlu nyin nigba keji, ati bi emi kò ti si lọdọ nyin nisisiyi, mo kọwe si awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ati si gbogbo awọn ẹlomiran, pe bi mo ba tún pada wá, emi kì yio da wọn si: 3 Niwọnbi ẹnyin ti nwá àmi Kristi ti nsọ̀rọ ninu mi, ẹniti ki iṣe ailera si nyin, ṣugbọn ti o jẹ agbara ninu nyin. 4 Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin. 5 Ẹ mã wadi ara nyin, bi ẹnyin bá wà ninu igbagbọ́; ẹ mã dan ara nyin wò. Tabi ẹnyin tikaranyin kò mọ̀ ara nyin pe Jesu Kristi wà ninu nyin? afi bi ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanù. 6 Ṣugbọn mo ni igbẹkẹle pe ẹnyin ó mọ̀ pe, awa kì iṣe awọn ti a tanù. 7 Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù. 8 Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ. 9 Nitori awa nyọ̀, nigbati awa jẹ alailera, ti ẹnyin si jẹ alagbara: eyi li awa si ngbadura fun pẹlu, ani pipe nyin. 10 Nitori idi eyi, nigbati emi kò si, mo kọwe nkan wọnyi pe, nigbati mo ba de, ki emi ki o má bã lò ikannú, gẹgẹ bi aṣẹ ti Oluwa ti fifun mi fun idagbasoke, kì si iṣe fun iparun.

Gbolohun Ìdágbére

11 Li akotan, ará, odigboṣe. Ẹ jẹ pipé, ẹ tújuka, ẹ jẹ oninu kan, ẹ mã wà li alafia; Ọlọrun ifẹ ati ti alafia yio wà pẹlu nyin. 12 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin. 13 Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin. 14 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati ìdapọ ti Ẹmí Mimọ́, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Galatia 1

Ìkíni

1 PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú), 2 Ati gbogbo awọn arakunrin ti o wà pẹlu mi, si awọn ijọ Galatia: 3 Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Jesu Kristi Oluwa wa, 4 Ẹniti o fi on tikalarẹ̀ fun ẹ̀ṣẹ wa, ki o le gbà wa kuro ninu aiye buburu isisiyi, gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun ati Baba wa: 5 Ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.

Kò Sí Ìyìn Rere Mìíràn

6 Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pè nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran: 7 Eyiti kì iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada. 8 Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. 9 Bi awa ti wi ṣaju, bẹ̃ni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. 10 Njẹ nisisiyi enia ni emi nyi lọkàn pada tabi Ọlọrun? tabi enia ni emi nfẹ lati wù? nitoripe bi emi ba si nwù enia, emi kì yio le ṣe iranṣẹ Kristi.

Bí Paulu ti Ṣe Di Aposteli

11 Ṣugbọn, ará, mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe ihinrere ti mo ti wasu kì iṣe nipa ti enia. 12 Nitori kì iṣe lọwọ enia ni mo ti gbà a, bẹ̃li a kò fi kọ́ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kristi. 13 Nitori ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ãlà, ti mo si bà a jẹ: 14 Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi. 15 Ṣugbọn nigbati o wù Ọlọrun, ẹniti o yà mi sọtọ lati inu iya mi wá, ti o si pè mi nipa ore-ọfẹ rẹ̀, 16 Lati fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, ki emi le mã wasu rẹ̀ larin awọn Keferi; lojukanna emi kò bá ara ati ẹ̀jẹ gbìmọ pọ̀: 17 Bẹ̃ni emi kò gòke lọ si Jerusalemu tọ̀ awọn ti iṣe Aposteli ṣaju mi; ṣugbọn mo lọ si Arabia, mo si tún pada wá si Damasku. 18 Lẹhin ọdún mẹta, nigbana ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ kí Peteru, mo si gbé ọdọ rẹ̀ ni ijọ mẹdogun. 19 Ṣugbọn emi kò ri ẹlomiran ninu awọn Aposteli miran, bikoṣe Jakọbu arakunrin Oluwa. 20 Nkan ti emi nkọ̀we si nyin yi, kiyesi i, niwaju Ọlọrun emi kò ṣeke. 21 Lẹhin na mo si wá si ẹkùn Siria ati ti Kilikia; 22 Mo sì jẹ ẹniti a kò mọ̀ li oju fun awọn ijọ ti o wà ninu Kristi ni Judea: 23 Ṣugbọn kìki nwọn ti gbọ́ pe, Ẹniti o ti nṣe inunibini si wa rí, si nwasu igbagbọ́ na nisisiyi, ti o ti mbajẹ nigbakan rí. 24 Nwọn si nyin Ọlọrun logo nitori mi.

Galatia 2

Àwọn Aposteli Yòókù Gba Paulu Bí Aposteli

1 LẸHIN ọdún mẹrinla, nigbana ni mo tún gòke lọ si Jerusalemu pẹlu Barnaba, mo si mu Titu lọ pẹlu mi. 2 Mo si gòke lọ nipa ifihan, mo si gbe ihinrere na kalẹ niwaju wọn ti mo nwasu larin awọn Keferi, ṣugbọn nikọ̀kọ fun awọn ti o jẹ ẹni-nla, ki emi kì o má ba sáre, tabi ki o má ba jẹ pe mo ti sáre lasan. 3 Ṣugbọn a kò fi agbara mu Titu ti o wà pẹlu mi, ẹniti iṣe ara Hellene, lati kọla: 4 Ati nitori awọn eke arakunrin ti a yọ́ mu wọ̀ inu wa wá, awọn ẹniti o yọ́ wa iṣe amí lati ri omnira wa, ti awa ni ninu Kristi Jesu, ki nwọn ki o le mu wa wá sinu ìde: 5 Awọn ẹniti awa kò si fi àye fun lati dari wa fun wakati kan; ki otitọ ìhinrere ki o le mã wà titi pẹlu nyin. 6 Ṣugbọn niti awọn ti o dabi ẹni nla, ohunkohun ti o wù ki nwọn jasi, kò jẹ nkankan fun mi: Ọlọrun kò ṣe ojuṣãju ẹnikẹni: ani awọn ti o dabi ẹni-nla, kò kọ́ mi ni nkankan. 7 Ṣugbọn kàkà bẹ̃, nigbati nwọn ri pe a ti fi ihinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi ihinrere ti awọn onila le Peteru lọwọ; 8 (Nitori ẹniti o ṣiṣẹ ninu Peteru si iṣẹ Aposteli ti ikọla, on kanna li o ṣiṣẹ ninu mi fun awọn Keferi pẹlu), 9 Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́ ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila. 10 Kìki nwọn fẹ ki a mã ranti awọn talakà, ohun kanna gan ti mo nfi titaratitara ṣe pẹlu.

Paulu Bá Peteru Wí ní Antioku

11 Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi. 12 Nitoripe ki awọn kan ti o ti ọdọ Jakọbu wá to de, o ti mba awọn Keferi jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn de, o fà sẹhin, o si yà ara rẹ̀ si apakan, o mbẹ̀ru awọn ti iṣe onila. 13 Awọn Ju ti o kù si jùmọ ṣe agabagebe bẹ̃ gẹgẹ pẹlu rẹ̀; tobẹ̃ ti nwọn si fi agabagebe wọn fà Barnaba tikararẹ lọ. 14 Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi lati mã rìn bi awọn Ju?

Igbagbọ Ni Ọ̀nà Ìgbàlà fún Gbogbo Eniyan

15 Awa ti iṣe Ju nipa ẹda, ti kì si iṣe ẹlẹṣẹ ti awọn Keferi, 16 Ti a mọ̀ pe a ko da ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, ani awa na gbà Jesu Kristi gbọ́, ki a ba le da wa lare nipa igbagbọ́ ti Kristi, kì si iṣe nipa iṣẹ ofin: nitoripe nipa iṣẹ ofin kò si enia kan ti a o dalare. 17 Ṣugbọn nigbati awa ba nwá ọ̀na lati ri idalare nipa Kristi, bi a ba si ri awa tikarawa li ẹlẹṣẹ, njẹ́ Kristi ha nṣe iranṣẹ ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri. 18 Nitoripe bi mo ba si tun gbe ohun wọnni ti mo ti wó palẹ ró, mo fi ara mi han bi arufin. 19 Nitoripe nipa ofin mo ti di oku si ofin, ki emi ki o le wà lãye si Ọlọrun. 20 A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lãye, sibẹ ki iṣe emi mọ́, ṣugbọn Kristi wà lãye ninu mi: wiwà ti mo si wà lãye ninu ara, mo wa lãye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararẹ̀ fun mi. 21 Emi kò sọ ore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitoripe bi ododo ba ti ipa ofin wá, njẹ Kristi kú lasan.

Galatia 3

Òfin tabi Igbagbọ

1 ẸNYIN alaironu ara Galatia, tani ha tàn nyin jẹ, ki ẹnyin ki o máṣe gbà otitọ gbọ́, li oju ẹniti a fi Jesu Kristi hàn gbangba lãrin nyin li ẹniti a kàn mọ agbelebu. 2 Kìki eyi ni mo fẹ mọ̀ lọwọ nyin pe, Nipa iṣẹ ofin li ẹnyin gbà Ẹmí bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́? 3 Bayi li ẹnyin ṣe alaironu to? ẹnyin ti o ti bẹ̀rẹ nipa ti Ẹmí a ha ṣe nyin pé nisisiyi nipa ti ara? 4 Ẹnyin ha ti jìya ọ̀pọlọpọ nkan wọnni lasan? bi o tilẹ ṣepe lasan ni. 5 Nitorina ẹniti o fun nyin li Ẹmí na, ti o si ṣe iṣẹ-agbara larin nyin, nipa iṣẹ ofin li o fi nṣe e bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́? 6 Gẹgẹ bi Abrahamu ti gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si fun u li ododo. 7 Nitorina ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ́, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu. 8 Bi iwe-mimọ́ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède. 9 Gẹgẹ bẹ̃li awọn ti iṣe ti igbagbọ́ jẹ ẹni alabukún-fun pẹlu Abrahamu olododo. 10 Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn. 11 Nitori o daniloju pe, a kò da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ofin: nitoripe, Olododo yio yè nipa igbagbọ́. 12 Ofin kì si iṣe ti igbagbọ́: ṣugbọn Ẹniti nṣe wọn yio yè nipasẹ wọn. 13 Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹniti a fi ṣe egun fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kọ́ sori igi: 14 Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́.

Òfin ati Ìlérí

15 Ará, emi nsọ̀rọ bi enia; bi o tilẹ jẹ pe majẹmu enia ni, ṣugbọn bi a ba ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò si ẹniti o le sọ ọ di asan, tabi ti o le fi kún u mọ́. 16 Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi. 17 Eyi ni mo nwipe, majẹmu ti Ọlọrun ti fi idi rẹ̀ mulẹ niṣãju, ofin ti o de lẹhin ọgbọ̀n-le-nirinwo ọdún kò le sọ ọ di asan, ti a ba fi mu ileri na di alailagbara. 18 Nitori bi ijogun na ba ṣe ti ofin, kì iṣe ti ileri mọ́: ṣugbọn Ọlọrun ti fi i fun Abrahamu nipa ileri. 19 Njẹ ki ha li ofin? a fi kun u nitori irekọja titi irú-ọmọ ti a ti ṣe ileri fun yio fi de; a si ti ipasẹ awọn angẹli ṣe ìlana rẹ̀ lati ọwọ́ alarina kan wá. 20 Njẹ alarina kì iṣe alarina ti ẹnikan, ṣugbọn ọ̀kan li Ọlọrun.

Ọmọ ati Ẹrú

21 Nitorina ofin ha lodi si awọn ileri Ọlọrun bi? Ki a má ri: nitori ibaṣepe a ti fi ofin kan funni, ti o lagbara lati sọni di ãye, nitotọ ododo iba ti ti ipasẹ ofin wá. 22 Ṣugbọn iwe-mimọ́ ti sé gbogbo nkan mọ́ sabẹ ẹ̀ṣẹ, ki a le fi ileri nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi fun awọn ti o gbagbọ́. 23 Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn. 24 Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́. 25 Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́. 26 Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. 27 Nitoripe iye ẹnyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ̀. 28 Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu. 29 Bi ẹnyin ba si jẹ ti Kristi, njẹ ẹnyin ni irú-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri.

Galatia 4

1 NJẸ mo wipe, niwọn igbati arole na ba wà li ewe, kò yàtọ ninu ohunkohun si ẹrú bi o tilẹ jẹ oluwa ohun gbogbo; 2 Ṣugbọn o wà labẹ olutọju ati iriju titi fi di akokò ti baba ti yàn tẹlẹ. 3 Gẹgẹ bẹ̃ si li awa, nigbati awa wà li ewe, awa wà li ondè labẹ ipilẹṣẹ ẹda: 4 Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin, 5 Lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gbà isọdọmọ. 6 Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba. 7 Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi.

Paulu Ní Àníyàn fún Àwọn Ará Galatia

8 Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda. 9 Ṣugbọn nisisiyi, nigbati ẹnyin ti mọ̀ Ọlọrun tan, tabi ki a sá kuku wipe, ẹ di mimọ̀ fun Ọlọrun, ẽha ti ri ti ẹ fi tun yipada si alailera ati alagbe ipilẹṣẹ ẹda, labẹ eyiti ẹnyin tun fẹ pada wa sinru? 10 Ẹnyin nkiyesi ọjọ, ati oṣù, ati akokò, ati ọdún. 11 Ẹru nyin mba mi, ki o má ba ṣe pe lasan ni mo ti ṣe lãlã lori nyin. 12 Ará, mo bẹ̀ nyin, ẹ dà bi emi; nitori emi dà bi ẹnyin: ẹnyin kò ṣe mi ni ibi kan. 13 Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe. 14 Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu. 15 Njẹ ayọ nyin igbana ha da? nitori mo gbà ẹ̀ri nyin jẹ pe, iba ṣe iṣe, ẹ ba yọ oju nyin jade, ẹ ba si fi wọn fun mi. 16 Njẹ mo ha di ọta nyin nitori mo sọ otitọ fun nyin bi? 17 Nwọn nfi itara wá nyin, ṣugbọn ki iṣe fun rere; nwọn nfẹ já nyin kuro, ki ẹnyin ki o le mã wá wọn. 18 Ṣugbọn o dara lati mã fi itara wá ni fun rere nigbagbogbo, kì si iṣe nigbati mo wà pẹlu nyin nikan. 19 Ẹnyin ọmọ mi kekeke, ẹnyin ti mo tún nrọbi titi a o fi ṣe ẹda Kristi ninu nyin. 20 Iba wù mi lati wà lọdọ nyin nisisiyi, ki emi ki o si yi ohùn mi pada nitoripe mo dãmu nitori nyin.

Àkàwé Hagari ati Sara

21 Ẹ wi fun mi, ẹnyin ti nfẹ wà labẹ ofin, ẹ kò ha gbọ́ ofin? 22 Nitori a ti kọ ọ pe, Abrahamu ni ọmọ ọkunrin meji, ọkan lati ọdọ ẹrú-binrin, ati ọkan lati ọdọ omnira-obinrin. 23 Ṣugbọn a bí eyiti iṣe ti ẹrúbinrin nipa ti ara; ṣugbọn eyi ti omnira-obinrin li a bí nipa ileri. 24 Nkan wọnyi jẹ apẹrẹ: nitoripe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeji; ọkan lati ori oke Sinai wá, ti a bí li oko-ẹrú, ti iṣe Hagari. 25 Nitori Hagari yi ni òke Sinai Arabia, ti o si duro fun Jerusalemu ti o wà nisisiyi, ti o si wà li oko-ẹrú pẹlu awọn ọmọ rẹ̀. 26 Ṣugbọn Jerusalemu ti oke jẹ omnira, eyiti iṣe iya wa. 27 Nitori a ti kọ ọ pe, Mã yọ̀, iwọ àgan ti kò bímọ: bú si ayọ̀ ki o si kigbe soke, iwọ ti kò rọbi rí; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ jù ti abilekọ lọ. 28 Njẹ ará, ọmọ ileri li awa gẹgẹ bi Isaaki. 29 Ṣugbọn bi eyiti a bí nipa ti ara ti ṣe inunibini nigbana si eyiti a bí nipa ti Ẹmi, bẹ̃ si ni nisisiyi. 30 Ṣugbọn iwe-mimọ́ ha ti wi? Lé ẹrú-binrin na jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrú-binrin kì yio ba ọmọ omnira-obinrin jogun pọ̀. 31 Nitorina, ará, awa kì iṣe ọmọ ẹrú-binrin, bikoṣe ti omnira-obinrin.

Galatia 5

Òmìnira Onigbagbọ

1 NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú mọ́. 2 Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun. 3 Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́. 4 A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ. 5 Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. 6 Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ. 7 Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ? 8 Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá. 9 Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu. 10 Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ. 11 Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. 12 Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro. 13 Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin. 14 Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. 15 Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.

Èso Ti Ẹ̀mí ati Àwọn Iṣẹ́ Ti Ara

16 Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ. 17 Nitoriti ara nṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmí, ati Ẹmí lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ má ba le ṣe ohun ti ẹnyin nfẹ. 18 Ṣugbọn bi a ba nti ọwọ Ẹmí ṣamọna nyin, ẹnyin kò si labẹ ofin. 19 Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahàn, ti iṣe wọnyi; panṣaga, àgbere, ìwa-ẽri, wọ̀bia, 20 Ibọriṣa, oṣó, irira, ìja, ilara, ibinu, asọ, ìṣọtẹ, adamọ̀, 21 Arankàn, ipania, imutipara, iréde-oru, ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ rí pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun. 22 Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́, 23 Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni. 24 Awọn ti iṣe ti Kristi Jesu ti kàn ara mọ agbelebu ti on ti ifẹ ati ifẹkufẹ rẹ̀. 25 Bi awa ba wà lãye sipa ti Ẹmí, ẹ jẹ ki a si mã rìn nipa ti Ẹmí. 26 Ẹ máṣe jẹ ki a mã ṣogo-asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.

Galatia 6

Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́

1 ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu. 2 Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ. 3 Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ. 4 Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. 5 Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀. 6 Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni. 7 Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká. 8 Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun. 9 Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀. 10 Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.

Gbolohun Ìparí

11 Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin. 12 Iye awọn ti nfẹ ṣe aṣehan li ara, nwọn nrọ̀ nyin lati kọla; kiki nitoripe ki a ma ba ṣe inunibini si wọn nitori agbelebu Kristi. 13 Nitori awọn ti a kọ nilà pãpã kò pa ofin mọ́, ṣugbọn nwọn nfẹ mu nyin kọla, ki nwọn ki o le mã ṣogo ninu ara nyin. 14 Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye. 15 Nitoripe ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla, bikoṣe ẹda titun. 16 Iye awọn ti o si nrìn gẹgẹ bi ìwọn yi, alafia lori wọn ati ãnu, ati lori Israeli Ọlọrun. 17 Lati isisiyi lọ, ki ẹnikẹni máṣe yọ mi lẹnu mọ́: nitori emi nrù àpá Jesu Oluwa kiri li ara mi. 18 Ará, ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.

Efesu 1

Ìkínni

1 PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, si awọn enia mimọ́ ti o wà ni Efesu, ati si awọn onigbagbọ ninu Kristi Jesu: 2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa.

Ibukun ti Ẹ̀mí Nípa Kristi

3 Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi: 4 Ani gẹgẹ bi o ti yàn wa ninu rẹ̀ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ki awa ki o le jẹ mimọ́ ati alailabùku niwaju rẹ̀ ninu ifẹ: 5 Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀: 6 Fun iyin ogo ore-ọfẹ rẹ̀, eyiti o dà lù wa ninu Ayanfẹ nì: 7 Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀; 8 Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye, 9 Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, 10 Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀: 11 Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀: 12 Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi; 13 Ninu ẹniti, ẹnyin pẹlu, nigbati ẹnyin ti gbọ ọrọ otitọ nì, ihinrere igbala nyin, ninu ẹniti nigbati ẹnyin ti gbagbọ pẹlu, a fi Ẹmi Mimọ́ ileri nì ṣe edidi nyin, 14 Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.

Adura Paulu

15 Nitori eyi, emi pẹlu, nigbati mo ti gburó igbagbọ ti mbẹ larin nyin ninu Jesu Oluwa, ati ifẹ nyin si gbogbo awọn enia mimọ́, 16 Emi kò si simi lati mã dupẹ nitori nyin, ati lati mã darukọ nyin ninu adura mi; 17 Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀: 18 Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ, 19 Ati agbara rẹ̀ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ́, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, 20 Eyiti o ti ṣiṣẹ ninu Kristi, nigbati o ti jí dide kuro ninu okú, ti o si fi i joko li ọwọ́ ọtún ninu awọn ọrun, 21 Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu. 22 O si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀, o si ti fi i ṣe ori lori ohun gbogbo fun ijọ, 23 Eyiti iṣe ara rẹ̀, ẹkún ẹniti o kún ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.

Efesu 2

Láti Inú Ikú sí Inú Ìyè

1 ẸNYIN li a si ti sọ di àye, nigbati ẹnyin ti kú nitori irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin, 2 Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran: 3 Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu. 4 Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa, 5 Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là). 6 O si ti ji wa dide pẹlu rẹ̀, o si ti mu wa wa joko pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun ninu Kristi Jesu: 7 Pe ni gbogbo ìgba ti mbọ ki o ba le fi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀ ti o pọ rekọja han ninu iṣeun rẹ̀ si wa ninu Kristi Jesu. 8 Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni: 9 Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo. 10 Nitori awa ni iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ ti a ti dá ninu Kristi Jesu fun iṣẹ rere, ti Ọlọrun ti pèse tẹlẹ, ki awa ki o le mã rìn ninu wọn.

Ọ̀kan ninu Kristi

11 Nitorina ẹ ranti pe, nigba atijọ ri, ẹnyin ti ẹ ti jẹ Keferi nipa ti ara, ti awọn ti a npè ni Akọla ti a fi ọwọ ṣe li ara npè li Alaikọla, 12 Pe li akokò na ẹnyin wà laini Kristi, ẹ jẹ ajeji si anfani awọn ọlọtọ Israeli, ati alejo si awọn majẹmu ileri nì, laini ireti, ati laini Ọlọrun li aiye: 13 Ṣugbọn nisisiyi ninu Kristi Jesu ẹnyin ti o ti jìna réré nigba atijọ rí li a mu sunmọ tosi, nipa ẹ̀jẹ Kristi. 14 Nitori on ni alafia wa, ẹniti o ti ṣe mejeji li ọ̀kan, ti o si ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lãrin; 15 O si ti fi opin si ọta nì ninu ara rẹ̀, ani si ofin aṣẹ wọnni ti mbẹ ninu ilana; ki o le fi awọn mejeji dá ẹni titun kan ninu ara rẹ̀, ki o si ṣe ilaja, 16 Ati ki o le mu awọn mejeji ba Ọlọrun làja ninu ara kan nipa agbelebu; o si ti pa iṣọta na kú nipa rẹ̀: 17 O si ti wá, o si ti wasu alafia fun ẹnyin ti o jìna réré, ati fun awọn ti o sunmọ tosi: 18 Nitori nipa rẹ̀ li awa mejeji ti ni ọ̀na nipa Ẹmí kan sọdọ Baba. 19 Njẹ nitorina ẹnyin kì iṣe alejò ati atipo mọ́, ṣugbọn àjumọ jẹ ọlọ̀tọ pẹlu awọn enia mimọ́, ati awọn ará ile Ọlọrun; 20 A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀ jẹ pàtaki okuta igun ile; 21 Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa: 22 Ninu ẹniti a ngbé nyin ró pọ pẹlu fun ibujoko Ọlọrun ninu Ẹmí.

Efesu 3

Iṣẹ́ Paulu láàrin Àwọn Tí Kì í Ṣe Juu

1 NITORI eyina, emi Paulu, ondè Jesu Kristi nitori ẹnyin Keferi, 2 Bi ẹnyin ba ti gbọ ti iṣẹ iriju ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun mi fun nyin: 3 Bi o ti ṣepe nipa ifihan li o ti fi ohun ijinlẹ nì hàn fun mi, (gẹgẹ bi mo ti kọ ṣaju li ọrọ diẹ, 4 Nigbati ẹnyin ba kà a, nipa eyi ti ẹnyin ó fi le mọ oye mi ninu ijinlẹ Kristi,) 5 Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí; 6 Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere: 7 Iranṣẹ eyiti a fi mi ṣe gẹgẹ bi ẹ̀bun ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀. 8 Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi; 9 Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ-iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ́ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi: 10 Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ, 11 Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa: 12 Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀. 13 Nitorina mo bẹ̀ nyin ki ãrẹ̀ ki o máṣe mu nyin ni gbogbo wahalà mi nitori nyin, ti iṣe ogo nyin.

Ìfẹ́ Tí Kristi Ní

14 Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, 15 Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye, 16 Ki on ki o le fifun nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ ogo rẹ̀, ki a le fi agbara rẹ̀ mú nyin li okun nipa Ẹmí rẹ̀ niti ẹni inu; 17 Ki Kristi ki o le mã gbé inu ọkàn nyin nipa igbagbọ; pe bi ẹ ti nfi gbongbo mulẹ, ti ẹ si nfi ẹsẹ mulẹ ninu ifẹ, 18 Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ, 19 Ati lati mọ ifẹ Kristi ti o ta ìmọ yọ, ki a le fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọrun kun nyin. 20 Njẹ ẹniti o le ṣe lọpọlọpọ jù gbogbo eyiti a mbère tabi ti a nrò lọ, gẹgẹ bi agbara ti nṣiṣẹ ninu wa, 21 On ni ki a mã fi ogo fun ninu ijọ ati ninu Kristi Jesu titi irandiran gbogbo, aiye ainipẹkun. Amin.

Efesu 4

Ìṣọ̀kan Ara Kristi

1 NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin, 2 Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin; 3 Ki ẹ si mã lakaka lati pa iṣọkan Ẹmí mọ́ ni ìdipọ alafia. 4 Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin; 5 Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan, 6 Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo. 7 Ṣugbọn olukuluku wa li a fi ore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹ̀bun Kristi. 8 Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia. 9 (Njẹ niti pe o goke lọ, kili o jẹ, bikoṣepe o kọ́ sọkalẹ pẹlu lọ si iha isalẹ ilẹ? 10 Ẹniti o ti sọkalẹ, on kanna li o si ti goke rekọja gbogbo awọn ọrun, ki o le kún ohun gbogbo.) 11 O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni; 12 Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi: 13 Titi gbogbo wa yio fi de iṣọkan igbagbọ́ ati ìmọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ọkunrin, titi a o fi de iwọn gigun ẹ̀kún Kristi: 14 Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina; 15 Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi: 16 Lati ọdọ ẹniti ara na ti a nso ṣọkan pọ, ti o si nfi ara mọra, nipa gbogbo orike ipese, (gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku ẹya-ara ni ìwọn tirẹ̀) o nmu ara na bi si i fun idagbasoke on tikararẹ ninu ifẹ.

Ìgbé-Ayé ti Àtijọ́ ati ti Ìsinsìnyìí

17 Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn, 18 Òye awọn ẹniti o ṣòkunkun, awọn ti o si ti di àjeji si ìwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ̀ ti mbẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn: 19 Awọn ẹniti ọkàn wọn le rekọja, ti nwọn si ti fi ara wọn fun wọ̀bia, lati mã fi iwọra ṣiṣẹ ìwa-ẽri gbogbo. 20 Ṣugbọn a kò fi Kristi kọ́ nyin bẹ̃; 21 Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu: 22 Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan; 23 Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin; 24 Ki ẹ si gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a da nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ́ otitọ́.

Ìlànà fún Ìgbé-Ayé Titun

25 Nitorina ẹ fi eke ṣiṣe silẹ, ki olukuluku nyin ki o mã ba ọmọnikeji rẹ̀ sọ otitọ, nitori ẹ̀ya-ara ọmọnikeji wa li awa iṣe. 26 Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin: 27 Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu. 28 Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini. 29 Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́. 30 Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande. 31 Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn: 32 Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.

Efesu 5

Gbígbé Ninu Ìmọ́lẹ̀

1 NITORINA ẹ mã ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n; 2 Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun. 3 Ṣugbọn àgbere, ati gbogbo ìwa ẽrí, tabi ojukòkoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ larin nyin mọ́, bi o ti yẹ awọn enia mimọ́; 4 Ibã ṣe ìwa ọ̀bun, ati isọ̀rọ wère, tabi iṣẹ̀fẹ, awọn ohun ti kò tọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã dupẹ. 5 Nitori ẹnyin mọ̀ eyi daju pe, kò si panṣaga, tabi alaimọ́ enia, tabi olojukòkoro, ti iṣe olubọriṣa, ti yio ni ini kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.

Ìwà Ọmọ Ìmọ́lẹ̀

6 Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi ọ̀rọ asan tàn nyin jẹ: nitori nipasẹ nkan wọnyi ibinu Ọlọrun mbọ̀ wá sori awọn ọmọ alaigbọran. 7 Nitorina ẹ máṣe jẹ alajọpin pẹlu wọn. 8 Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ: 9 (Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;) 10 Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa. 11 Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi. 12 Nitori itiju tilẹ ni lati mã sọ̀rọ nkan wọnni ti nwọn nṣe nikọ̀kọ. 13 Ṣugbọn ohun gbogbo ti a mba wi ni imọlẹ ifi han: nitori ohunkohun ti o ba fi nkan hàn, imọlẹ ni. 14 Nitorina li o ṣe wipe, Jí, iwọ ẹniti o sùn, si jinde kuro ninu okú, Kristi yio si fun ọ ni imọlẹ. 15 Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; 16 Ẹ mã ra ìgba pada, nitori buburu li awọn ọjọ. 17 Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi. 18 Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí; 19 Ẹ si mã bá ara nyin sọ̀rọ ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã kọrin, ki ẹ si mã kọrin didun li ọkàn nyin si Oluwa; 20 Ẹ mã dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa;

Aya ati Ọkọ

21 Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun. 22 Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi fun Oluwa. 23 Nitoripe ọkọ ni iṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi ti ṣe ori ijọ enia rẹ̀: on si ni Olugbala ara. 24 Nitorina gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹ̃ si ni ki awọn aya ki o mã ṣe si ọkọ wọn li ohun gbogbo. 25 Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u; 26 Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi, 27 Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku. 28 Bẹ̃li o tọ́ ki awọn ọkunrin ki o mã fẹràn awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn. Ẹniti o ba fẹran aya rẹ̀, o fẹran on tikararẹ̀. 29 Nitori kò si ẹnikan ti o ti korira ara rẹ̀; bikoṣepe ki o mã bọ́ ọ ki o si mã ṣikẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi si ti nṣe si ìjọ. 30 Nitoripe awa li ẹ̀ya-ara rẹ̀, ati ti ẹran-ara rẹ̀, ati ti egungun ara rẹ̀. 31 Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, on o si dàpọ mọ́ aya rẹ̀, awọn mejeji a si di ara kan. 32 Aṣiri nla li eyi: ṣugbọn emi nsọ nipa ti Kristi ati ti ijọ. 33 Ṣugbọn ki olukuluku nyin ki o fẹran aya rẹ̀ bẹ̃ gẹgẹ bi on tikararẹ̀; ki aya ki o si bẹru ọkọ rẹ̀.

Efesu 6

Ọmọ ati Òbí

1 ẸNYIN ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́. 2 Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri), 3 Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye. 4 Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mã tọ́ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.

Ẹrú ati Ọ̀gá

5 Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mã gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwarìri, ni otitọ ọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi; 6 Ki iṣe ti arojuṣe bi awọn ti nwù enia; ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ mã ṣe ifẹ Ọlọrun lati inu wá; 7 Ẹ mã fi inu rere sin bi si Oluwa, kì si iṣe si enia: 8 Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira. 9 Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀.

Ìjàkadì pẹlu Ibi

10 Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu. 12 Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun. 13 Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro. 14 Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra; 15 Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ̀ ẹsẹ nyin ni bàta; 16 Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì. 17 Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmí, ti iṣe ọ̀rọ Ọlọrun: 18 Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́; 19 Ati fun mi, ki a le fi ohùn fun mi, ki emi ki o le mã fi igboiya yà ẹnu mi, lati mã fi ohun ijinlẹ ihinrere hàn, 20 Nitori eyiti emi jẹ ikọ̀ ninu ẹ̀wọn: ki emi ki o le mã fi igboiya sọ̀rọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ.

Gbolohun Ìparí

21 Ṣugbọn ki ẹnyin pẹlu ki o le mọ̀ bi nkan ti ri fun mi, bi mo ti nṣe si, Tikiku arakunrin olufẹ ati iranṣẹ olõtọ ninu Oluwa, yio sọ ohun gbogbo di mimọ̀ fun nyin: 22 Ẹniti mo rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹ le mọ bi a ti wà, ki on ki o le tu ọkàn nyin ninu. 23 Alafia fun awọn ará, ati ifẹ pẹlu igbagbọ́, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Oluwa Jesu Kristi. 24 Ki ore-ọfẹ wà pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ Oluwa wa Jesu Kristi li aiṣẹ̀tan.

Filippi 1

Ìkíni

1 PAULU ati Timotiu, awọn iranṣẹ Jesu Kristi, si gbogbo awọn enia mimọ́ ninu Kristi Jesu ti o wà ni Filippi, pẹlu awọn biṣopu ati awọn diakoni: 2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi.

Adura fún Àwọn Ará Filipi

3 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe, 4 Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ̀ bẹ̀bẹ, 5 Nitori ìdapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ kini wá titi fi di isisiyi. 6 Ohun kan yi sa da mi loju, pe ẹniti o ti bẹ̀rẹ iṣẹ rere ninu nyin, yio ṣe aṣepe rẹ̀ titi fi di ọjọ Jesu Kristi: 7 Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere. 8 Nitori Ọlọrun li ẹlẹri mi, bi mo ti nṣafẹri nyin to gidigidi ninu iyọ́nu Jesu Kristi. 9 Eyi si ni mo ngbadura fun pe, ki ifẹ nyin ki o le mã pọ si i siwaju ati siwaju ninu imọ̀ ati imoye gbogbo. 10 Ki ẹnyin ki o le dán ohun ti o yàtọ wò; ki ẹ si jasi olododo ati alaijẹ-ohun-ikọsẹ titi fi di ọjọ Jesu Kristi; 11 Lẹhin igbati ẹ ti kun fun eso ododo lati ọdọ Jesu Kristi, fun ogo ati iyìn Ọlọrun.

Ìgbé-Ayé ninu Kristi

12 Njẹ emi fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀, ará, pe nkan wọnni ti o de bá mi, o kuku yọri si ilọsiwaju ihinrere; 13 Tobẹ ti idè mi gbogbo farahan ninu Kristi larin awọn ọmọ-ogun ãfin ati gbogbo awọn ẹlomiran; 14 Ati pe ọ̀pọlọpọ awọn arakunrin ninu Oluwa, ti o ni igbẹkẹle si ìde mi nfi igboiya gidigidi sọrọ Ọlọrun laibẹru. 15 Nitotọ awọn ẹlomiran tilẹ nfi ija ati ilara wasu Kristi; awọn ẹlomiran si nfi inu rere ṣe e. 16 Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi: 17 Awọn kan ẹwẹ si nfi ifẹ ṣe e, nitoriti nwọn mọ̀ pe a gbe mi dide fun idahun-ẹjọ ihinrere. 18 Njẹ kini? bikoṣepe nibi gbogbo, iba ṣe niti àfẹ̀tànṣe tabi niti otitọ, a sa nwasu Kristi; emi si nyọ̀ nitorina, nitõtọ, emi ó si ma yọ̀. 19 Nitoriti mo mọ̀ pe eyi ni yio yọri si igbala fun mi lati inu adura nyin wá, ati ifikún Ẹmí Jesu Kristi, 20 Gẹgẹ bi ìnàgà ati ireti mi pe ki oju ki o máṣe tì mi li ohunkohun, ṣugbọn pẹlu igboiya gbogbo, bi nigbagbogbo, bẹ̃ nisisiyi pẹlu a o gbé Kristi ga lara mi, ibã ṣe nipa ìye, tabi nipa ikú. 21 Nitori, niti emi, lati wà lãye jẹ Kristi, lati kú jẹ ere. 22 Ṣugbọn bi lati wà lãye ninu ara ba jẹ eso iṣẹ mi, nigbana ohun ti emi o yàn, emi kò mọ. 23 Ṣugbọn emi mbẹ ni iyemeji, mo ni ifẹ lati lọ ati lati wà lọdọ Kristi; nitori o dara pupọ ju: 24 Sibẹ lati wà ninu ara jẹ anfani nitori ti nyin. 25 Bi eyi si ti da mi loju, mo mọ̀ pe emi ó duro, emi ó si mã bá gbogbo nyin gbé fun ilọsiwaju ati ayọ̀ nyin ninu igbagbọ; 26 Ki iṣogo nyin ki o le di pupọ gidigidi ninu Jesu Kristi ninu mi nipa ipada wá mi sọdọ nyin. 27 Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan; 28 Ki ẹ má si jẹ ki awọn ọta dẹruba nyin li ohunkohun: eyiti iṣe àmi ti o daju fun iparun wọn, ṣugbọn ti igbala nyin, ati eyini ni lati ọwọ́ Ọlọrun wá. 29 Nitori niti Kristi, ẹnyin li a ti yọnda fun, kì iṣe lati gbà a gbọ́ nikan, ṣugbọn lati jìya nitori rẹ̀ pẹlu: 30 Ẹ si ni ìja kanna ti ẹnyin ti ri ninu mi, ti ẹnyin si gbọ́ nisisiyi pe o wà ninu mi.

Filippi 2

Jesu Rẹ Ara Rẹ̀ Sílẹ̀

1 NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà, 2 Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan. 3 Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ. 4 Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran. 5 Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: 6 Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: 7 Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia. 8 Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu. 9 Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ: 10 Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ; 11 Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.

Onigbagbọ Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ ninu Ayé

12 Nitorina ẹnyin olufẹ mi, gẹgẹ bi ẹnyin ti ngbọran nigbagbogbo, kì iṣe nigbati mo wà lọdọ nyin nikan, ṣugbọn papa nisisiyi ti emi kò si, ẹ mã ṣiṣẹ igbala nyin yọri pẹlu ìbẹru ati iwarìri, 13 Nitoripe Ọlọrun ni nṣiṣẹ ninu nyin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ifẹ inu rere rẹ̀. 14 Ẹ mã ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan. 15 Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye; 16 Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan. 17 Ani, bi a tilẹ tú mi dà sori ẹbọ ati iṣẹ isin igbagbọ́ nyin, mo yọ̀, mo si mba gbogbo nyin yọ̀ pẹlu. 18 Bakanna ni ki ẹnyin ki o mã yọ̀, ki ẹ si mã ba mi yọ̀ pẹlu.

Timotiu ati Epafiroditu

19 Ṣugbọn mo ni ireti ninu Jesu Oluwa, lati rán Timotiu si nyin ni lọ̃lọ yi, ki emi pẹlu le ni ifọkanbalẹ nigbati mo ba gburó ijoko nyin. 20 Nitori emi kò ni ẹni oninu kanna ti o dabi rẹ̀, ti yio ma fi tinutinu ṣe aniyan nyin. 21 Nitori gbogbo wọn ni ntọju nkan ti ara wọn, kì iṣe nkan ti iṣe ti Jesu Kristi. 22 Ṣugbọn ẹnyin ti mọ̀ ọ dajudaju, pe gẹgẹ bi ọmọ lọdọ baba rẹ̀, bẹ̃li o si ti mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere. 23 Nitorina on ni mo ni ireti lati rán si nyin nisisiyi, nigbati mo ba woye bi yio ti ri fun mi. 24 Ṣugbọn mo gbẹkẹle Oluwa, pe emi tikarami pẹlu yio wá ni lọ̃lọ. 25 Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi. 26 Nitoriti ọkàn rẹ̀ fà si gbogbo nyin, o si kún fun ibanujẹ, nitoriti ẹnyin ti gbọ́ pe on ti ṣe aisan. 27 Nitõtọ li o ti ṣe aisan titi de oju ikú: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣãnu fun u; kì si iṣe fun on nikan, ṣugbọn fun mi pẹlu, ki emi ki o màṣe ni ibanujẹ lori ibanujẹ. 28 Nitorina ni mo ṣe fi titara-titara rán a, pe nigbati ẹnyin ba si tún ri i, ki ẹnyin ki o le yọ̀, ati ki ibanujẹ mi ki o le dínkù. 29 Nitorina ẹ fi ayọ̀ pupọ gbà a nipa ti Oluwa; ki ẹ si ma bù ọlá fun irú awọn ẹni bẹ̃: 30 Nitoripe nitori iṣẹ Kristi li o ṣe sunmọ ẹnu-ọ̀na ikú, ti kò si kà ẹmí ara rẹ̀ si, lati mu aitó iṣẹ isin nyin si mi kun.

Filippi 3

Òdodo Tòótọ́

1 LI akotan, ará, ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa. Kì iṣe inira fun mi lati kọwe ohun kanna si nyin, ṣugbọn fun nyin o jẹ ailewu. 2 Ẹ kiyesara lọdọ awọn ajá, ẹ kiyesara lọdọ awọn oniṣẹ-buburu, ẹ kiyesara lọdọ awọn onilà. 3 Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara; 4 Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju: 5 Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi; 6 Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan. 7 Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi. 8 Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi, 9 Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́: 10 Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀; 11 Bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú.

Ète tí Ó Ga Jù lọ

12 Kì iṣe pe ọwọ mi ti tẹ ẹ na, tabi mo ti di pipé: ṣugbọn emi nlepa nṣo, bi ọwọ́ mi yio le tẹ̀ ère na, nitori eyiti a ti di mi mu pẹlu, lati ọdọ Kristi Jesu wá. 13 Ará emi kò kà ara mi si ẹniti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ na: ṣugbọn ohun kan yi li emi nṣe, emi ngbagbé awọn nkan ti o wà lẹhin, mo si nnàgà wò awọn nkan ti o wà niwaju, 14 Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu. 15 Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin. 16 Kiki pe, ibiti a ti de na, ẹ jẹ ki a mã rìn li oju ọna kanna, ki a ni ero kanna. 17 Ará, ẹ jumọ ṣe afarawe mi, ẹ si ṣe akiyesi awọn ti nrìn bẹ̃, ani bi ẹ ti ni wa fun apẹrẹ. 18 (Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn: 19 Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.) 20 Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa: 21 Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.

Filippi 4

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú

1 NITORINA, ẹnyin ará mi olufẹ, ti mo si nṣafẹri gidigidi, ayọ̀ ati ade mi, ẹ duro ṣinṣin bẹ̃ ninu Oluwa, ẹnyin olufẹ mi. 2 Emi mbẹ̀ Euodia, mo si mbẹ̀ Sintike, ki nwọn ni inu kanna ninu Oluwa. 3 Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye. 4 Ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa nigbagbogbo: mo si tún wi, Ẹ mã yọ̀. 5 Ẹ jẹ ki ipamọra nyin di mimọ̀ fun gbogbo enia. Oluwa mbẹ nitosi. 6 Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ìbere nyin hàn fun Ọlọrun. 7 Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu. 8 Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò. 9 Nkan wọnni, ti ẹnyin ti kọ́, ti ẹnyin si ti gbà, ti ẹnyin si ti gbọ́, ti ẹnyin si ti ri lọwọ mi, ẹ mã ṣe wọn: Ọlọrun alafia yio si wà pẹlu nyin.

Paulu Dúpẹ́ fún Ẹ̀bùn

10 Ṣugbọn emi yọ̀ gidigidi ninu Oluwa pe, asiwá-asibọ̀ ero nyin tun sọji fun mi, eyiti ẹ ti nro nitotọ, ṣugbọn ẹnyin kò ni akokò ti o wọ̀. 11 Kì iṣe pe emi nsọ nitori aini: nitoripe ipòkipo ti mo ba wà, mo ti kọ́ lati ni itẹlọrùn ninu rẹ̀. 12 Mo mọ̀ bi ã ti iṣe di rirẹ̀-silẹ, mo mọ bi ã ti iṣe di pupọ: li ohunkohun ati li ohun gbogbo mo ti kọ́ aṣiri ati mã jẹ ajẹyó ati lati wà li aijẹ, lati mã ni anijù ati lati ṣe alaini. 13 Emi le ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹniti nfi agbara fun mi. 14 Ṣugbọn ẹnyin ṣeun gidigidi niti pe ẹnyin ṣe alabapin ninu ipọnju mi. 15 Ẹnyin papa si mọ̀ pẹlu, ẹnyin ara Filippi, pe li ibẹrẹ ihinrere, nigbati mo kuro ni Makedonia, kò si ijọ kan ti o ba mi ṣe alabapin niti gbigbà ati fifunni, bikoṣe ẹnyin nikanṣoṣo. 16 Nitori ni Tessalonika gidi, ẹnyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ fun aini mi. 17 Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin. 18 Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun. 19 Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu. 20 Ṣugbọn ogo ni fun Ọlọrun ati Baba wa lai ati lailai. Amin.

Ìdágbére

21 Ẹ kí olukuluku enia mimọ́ ninu Kristi Jesu. Awọn ara ti o wà pẹlu mi kí nyin. 22 Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin, papa awọn ti iṣe ti agbo ile Kesari. 23 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmi nyin. Amin.

A kọ ọ si awọn ara Filippi lati Romu lọ lati ọwọ́ Epafroditu.

Kolosse 1

Ìkíni

1 PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, 2 Si awọn enia mimọ́ ati awọn ará wa olõtọ ninu Kristi ti o wà ni Kolosse: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

Adura Ọpẹ́

3 Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, awa si ngbadura fun nyin nigbagbogbo, 4 Nigbati awa gburó igbagbọ́ nyin ninu Kristi Jesu, ati ifẹ ti ẹnyin ni si gbogbo awọn enia mimọ́, 5 Nitori ireti ti a gbé kalẹ fun nyin li ọrun, nipa eyiti ẹnyin ti gbọ́ ṣaju ninu ọ̀rọ otitọ ti ihinrere, 6 Eyiti o de ọdọ nyin, ani bi o ti nso eso pẹlu ni gbogbo aiye ti o si npọ si i, bi o ti nṣe ninu nyin pẹlu, lati ọjọ ti ẹnyin ti gbọ́, ti ẹnyin si ti mọ̀ ore-ọfẹ Ọlọrun li otitọ: 7 Ani bi ẹnyin ti kọ́ lọdọ Epafra iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa olufẹ, ẹniti iṣe olõtọ iranṣẹ Kristi nipo wa, 8 Ti o si ròhin ifẹ nyin ninu Ẹmí fun wa pẹlu. 9 Nitori eyi, lati ọjọ ti awa ti gbọ, awa pẹlu kò simi lati mã gbadura ati lati mã bẹ̀bẹ fun nyin pe ki ẹnyin ki o le kún fun ìmọ ifẹ rẹ̀ ninu ọgbọ́n ati imoye gbogbo ti iṣe ti Ẹmí; 10 Ki ẹ le mã rìn ni yiyẹ niti Oluwa si ìwu gbogbo, ki ẹ ma so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ si mã pọ si i ninu ìmọ Ọlọrun; 11 Ki a fi ipá gbogbo sọ nyin di alagbara, gẹgẹ bi agbara ogo rẹ̀, sinu suru ati ipamọra gbogbo pẹlu ayọ̀;

Ẹni Tí Kristi Jẹ́ ati Iṣẹ́ Rẹ̀

12 Ki a mã dupẹ lọwọ Baba, ẹniti o mu wa yẹ lati jẹ alabapin ninu ogún awọn enia mimọ́ ninu imọlẹ: 13 Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀: 14 Ninu ẹniti awa ni idande nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, ani idariji ẹ̀ṣẹ: 15 Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda: 16 Nitori ninu rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ohun ti mbẹ li ọrun, ati ohun ti mbẹ li aiye, eyiti a ri, ati eyiti a kò ri, nwọn iba ṣe itẹ́, tabi oye, tabi ijọba, tabi ọla: nipasẹ rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u: 17 On si wà ṣaju ohun gbogbo, ati ninu rẹ̀ li ohun gbogbo duro ṣọkan. 18 On si jẹ ori fun ara, eyini ni ìjọ: ẹniti iṣe ipilẹṣẹ, akọbi lati inu okú wá; pe, ninu ohun gbogbo ki on ki o le ni ipò ti o ga julọ. 19 Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀; 20 Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun. 21 Ati ẹnyin ti o ti jẹ alejò ati ọtá rí li ọkàn nyin ni iṣẹ buburu nyin, ẹnyin li o si ti bá laja nisisiyi, 22 Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi; 23 Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun. 24 Nisisiyi emi nyọ̀ ninu ìya mi nitori nyin, emi si nmu ipọnju Kristi ti o kù lẹhin kún li ara mi, nitori ara rẹ̀, ti iṣe ìjọ: 25 Eyiti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fifun mi fun nyin lati mu ọ̀rọ Ọlọrun ṣẹ; 26 Ani ohun ijinlẹ ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihàn nisisiyi fun awọn enia mimọ́ rẹ̀: 27 Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo: 28 Ẹniti awa nwasu rẹ̀ ti a nkìlọ fun olukuluku enia, ti a si nkọ́ olukuluku enia ninu ọgbọ́n gbogbo; ki a le mu olukuluku enia wá ni ìwa pipé ninu Kristi Jesu: 29 Eyiti emi nṣe lãlã ti mo si njijakadi fun pẹlu, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, ti nfi agbara ṣiṣẹ gidigidi ninu mi.

Kolosse 2

1 NITORI emi nfẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ bi iwaya-ìja ti mo ni fun nyin ti pọ̀ to, ati fun awọn ará Laodikea, ati fun iye awọn ti kò ti iri oju mi nipa ti ara; 2 Ki a le tu ọkàn wọn ninu, bi a ti so wọn pọ̀ ninu ifẹ ati si gbogbo ọrọ̀ ẹ̀kún oye ti o daju, si imọ̀ ohun ijinlẹ Ọlọrun ani Kristi; 3 Inu ẹniti a ti fi gbogbo iṣura ọgbọ́n ati ti ìmọ pamọ́ si. 4 Eyi ni mo si nwi, ki ẹnikẹni ki o má bã fi ọ̀rọ ẹtàn mu nyin ṣina. 5 Nitoripe bi emi kò tilẹ si lọdọ nyin li ara, ṣugbọn emi mbẹ lọdọ nyin li ẹmí, mo nyọ̀, mo si nkiyesi eto nyin, ati iduroṣinṣin igbagbọ́ nyin ninu Kristi.

Ìgbé-Ayé Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu Kristi

6 Nitorina bi ẹnyin ti gbà Kristi Jesu Oluwa, bẹ̃ni ki ẹ mã rìn ninu rẹ̀: 7 Ki ẹ fi gbongbo mulẹ, ki a si gbe nyin ro ninu rẹ̀, ki ẹ si fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ nyin, gẹgẹ bi a ti kọ́ nyin, ki ẹ si mã pọ̀ ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ. 8 Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi. 9 Nitoripe ninu rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara. 10 A si ti ṣe nyin ni kikún ninu rẹ̀, ẹniti iṣe ori fun gbogbo ijọba ati agbara: 11 Ninu ẹniti a ti fi ikọla ti a kò fi ọwọ kọ kọ nyin ni ila, ni bibọ ara ẹ̀ṣẹ silẹ, ninu ikọla Kristi: 12 Bi a si ti sin nyin pọ̀ pẹlu rẹ̀ ninu baptismu, ninu eyiti a si ti jí nyin dide pẹlu rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu iṣẹ Ọlọrun, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú. 13 Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin; 14 O si ti pa iwe majẹmu nì rẹ́, ti o lodi si wa, ti a kọ ninu ofin, eyiti o lodi si wa: on li o si ti mu kuro loju ọ̀na, o si kàn a mọ agbelebu; 15 O si ti já awọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ̀ ayọ̀ iṣẹgun lori wọn ninu rẹ̀. 16 Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi: 17 Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara. 18 Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi adabọwọ irẹlẹ ati bibọ awọn angẹli lọ́ ere nyin gbà lọwọ nyin, ẹniti nduro lori nkan wọnni ti o ti ri, ti o nti ipa ero rẹ̀ niti ara ṣeféfe asan, 19 Ti kò si di Ori nì mu ṣinṣin, lati ọdọ ẹniti a nti ipa orike ati iṣan pese fun gbogbo ara, ti a si nso o ṣọkan pọ, ti o si ndagba nipa ibisi Ọlọrun.

Ìgbé-Ayé Titun ninu Kristi

20 Bi ẹnyin ba ti kú pẹlu Kristi kuro ninu ipilẹṣẹ aiye, ẽhatiṣe ti ẹnyin ntẹriba fun ofin bi ẹnipe ẹnyin wà ninu aiye, 21 Maṣe fọwọkàn, maṣe tọ́wò, maṣe fọwọbà, 22 (Gbogbo eyiti yio ti ipa lilo run), gẹgẹ bi ofin ati ẹkọ́ enia? 23 Awọn nkan ti o ni afarawe ọgbọ́n nitõtọ, ni adabọwọ ìsin, ati irẹlẹ, ati ìpọn-ara-loju, ṣugbọn ti kò ni ere kan ninu fun ifẹkufẹ ara.

Kolosse 3

1 NJẸ bi a ba ti ji nyin dide pẹlu Kristi, ẹ mã ṣafẹri awọn nkan ti mbẹ loke, nibiti Kristi gbé wà ti o joko li ọwọ́ ọtun Ọlọrun. 2 Ẹ mã ronu awọn nkan ti mbẹ loke kì iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye. 3 Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. 4 Nigbati Kristi, ẹniti iṣe ìye wa yio farahàn, nigbana li ẹnyin pẹlu o farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ogo. 5 Nitorina ẹ mã pa ẹ̀ya-ara nyin ti mbẹ li aiye run: àgbere, iwa-ẽri, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukòkoro, ti iṣe ibọriṣa: 6 Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran. 7 Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi. 8 Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin. 9 Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀; 10 Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a: 11 Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo. 12 Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra; 13 Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu. 14 Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé. 15 Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ. 16 Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa. 17 Ohunkohun ti ẹnyin ba si nṣe li ọ̀rọ tabi ni iṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn li orukọ Jesu Oluwa, ẹ mã fi ọpẹ́ fun Ọlọrun Baba nipasẹ rẹ̀.

Ìbálò Onigbagbọ pẹlu Ara Wọn

18 Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi o ti yẹ ninu Oluwa. 19 Ẹnyin ọkọ, ẹ mã fẹran awọn aya nyin, ẹ má si ṣe korò si wọn. 20 Ẹnyin ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin li ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa. 21 Ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu, ki nwọn má bã rẹwẹsi. 22 Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara li ohun gbogbo; kì iṣe ni arojuṣe, bi awọn alaṣewù enia; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹ̀ru Ọlọrun: 23 Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kì si iṣe fun enia; 24 Ki ẹ mọ̀ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbà ère ogun: nitori ẹnyin nsìn Oluwa Kristi. 25 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe aiṣododo, yio gbà pada nitori aiṣododo na ti o ti ṣe: kò si si ojuṣãju enia.

Kolosse 4

1 ẸNYIN oluwa, ẹ ma fi eyiti o tọ́ ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ̀ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú

2 Ẹ mã duro ṣinṣin ninu adura igbà, ki ẹ si mã ṣọra ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ; 3 Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu: 4 Ki emi ki o le fihan, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ. 5 Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba. 6 Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn.

Gbolohun Ìparí

7 Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: 8 Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu; 9 Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin. 10 Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a), 11 Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi. 12 Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun. 13 Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli. 14 Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin. 15 Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀. 16 Nigbati a ba si kà iwe yi larin nyin tan, ki ẹ mu ki a kà a pẹlu ninu ìjọ Laodikea; ki ẹnyin pẹlu si kà eyi ti o ti Laodikea wá. 17 Ki ẹ si wi fun Arkippu pe, Kiyesi iṣẹ-iranṣẹ ti iwọ ti gbà ninu Oluwa, ki o si ṣe e ni kikún. 18 Ikíni nipa ọwọ́ emi Paulu. Ẹ mã ranti ìde mi. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.

1 Tessalonika 1

Ìkíni

1 PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ awọn ara Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kristi Oluwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìdúpẹ́

2 Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo fun gbogbo nyin, awa nṣe iranti nyin ninu adura wa; 3 Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa; 4 Nitoripe awa mọ yiyan nyin, ara olufẹ ti Ọlọrun, 5 Bi ihinrere wa kò ti wá sọdọ nyin li ọ̀rọ nikan, ṣugbọn li agbara pẹlu, ati ninu Ẹmí Mimọ́, ati ni ọ̀pọlọpọ igbẹkẹle; bi ẹnyin ti mọ̀ irú enia ti awa jẹ́ larin nyin nitori nyin. 6 Ẹnyin si di alafarawe wa, ati ti Oluwa, lẹhin ti ẹnyin ti gbà ọ̀rọ na ninu ipọnju ọ̀pọlọpọ, pẹlu ayọ̀ Ẹmí Mimọ́: 7 Ti ẹnyin si jẹ apẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ́ ni Makedonia ati Akaia. 8 Nitori lati ọdọ nyin lọ li ọ̀rọ Oluwa ti dún jade, kì iṣe ni kìki Makedonia ati Akaia nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni ìhin igbagbọ́ nyin si Ọlọrun tàn kalẹ; tobẹ̃ ti awa kò ni isọ̀rọ ohunkohun. 9 Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ; 10 Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.

1 Tessalonika 2

Iṣẹ́ Paulu ní Tẹsalonika

1 NITORI ẹnyin tikaranyin mọ̀, ará, irú iwọle wa si nyin pe kì iṣe lasan: 2 Ṣugbọn lẹhin ti awa ti jìya ṣaju, ti a si ti lo wa ni ilo itiju ni Filippi gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, awa ni igboiya ninu Ọlọrun wa lati sọ̀rọ ihinrere Ọlọrun fun nyin pẹlu ọ̀pọlọpọ ìwàyá ìjà. 3 Nitori ọ̀rọ iyanju wa kì iṣe ti ẹ̀tan, tabi ti ìwa aimọ́, tabi ninu arekereke: 4 Ṣugbọn bi a ti kà wa yẹ lati ọdọ Ọlọrun wá bi ẹniti a fi ihinrere le lọwọ, bẹ̃ li awa nsọ; kì iṣe bi ẹniti nwù enia bikoṣe Ọlọrun, ti ndan ọkàn wa wò. 5 Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri: 6 Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi. 7 Ṣugbọn awa nṣe pẹlẹ lọdọ nyin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ntọju awọn ọmọ on tikararẹ: 8 Bẹ̃ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si nyin, inu wa dun jọjọ lati fun nyin kì iṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmí awa tikarawa pẹlu, nitoriti ẹnyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa. 9 Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin. 10 Ẹnyin si li ẹlẹri, ati Ọlọrun pẹlu, bi awa ti wà lãrin ẹnyin ti o gbagbọ́ ni mimọ́ iwà ati li ododo, ati li ailẹgan: 11 Gẹgẹ bi ẹnyin si ti mọ̀ bi awa ti mba olukuluku nyin lo gẹgẹ bi baba si awọn ọmọ rẹ̀, a ngba nyin niyanju, a ntu nyin ninu, a si kọ́, 12 Ki ẹnyin ki o le mã rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹniti o npè nyin sinu ijọba ati ogo On tikararẹ. 13 Nitori eyi li awa ṣe ndupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu li aisimi, pe nigbati ẹnyin gba ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ Ọlọrun, ẹnyin kò gbà a bi ẹnipe ọ̀rọ enia, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitõtọ, bi ọ̀rọ Ọlọrun, eyiti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹnyin ti o gbagbọ́ pẹlu. 14 Nitori, ará, ẹnyin di alafarawe awọn ijọ Ọlọrun ti mbẹ ni Judea, ninu Kristi Jesu: nitoripe ẹnyin pẹlu jìya iru ohun kanna lọwọ awọn ara ilu nyin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jìya lọwọ awọn Ju: 15 Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia: 16 Nwọn kọ̀ fun wa lati sọ̀rọ fun awọn Keferi ki nwọn ki o le là, lati mã sọ ẹ̀ṣẹ wọn di kikun nigbagbogbo: ṣugbọn ibinu de bá wọn titi de opin. 17 Ṣugbọn, ará, awa ti a gbà kuro lọdọ nyin fun sã kan li ara, ki iṣe li ọkàn, pẹlu itara ọpọlọpọ li awa ṣe aniyan ti a si fẹ gidigidi lati ri oju nyin. 18 Nitori awa fẹ lati tọ̀ nyin wá, ani emi Paulu lẹ̃kini ati lẹ̃keji; Satani si dè wa li ọ̀na. 19 Nitori kini ireti wa, tabi ayọ̀ wa, tabi ade iṣogo wa? kì ha iṣe ẹnyin ni niwaju Jesu Oluwa wa ni àbọ rẹ̀? 20 Nitori ẹnyin ni ogo ati ayọ̀ wa.

1 Tessalonika 3

1 NITORINA nigbati ara wa kò gba a mọ́, awa rò pe o dara ki a fi awa nikan sẹhin ni Ateni; 2 Awa si rán Timotiu, arakunrin wa, ati iranṣẹ Ọlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ nyin mulẹ, ati lati tù nyin ninu niti igbagbọ́ nyin: 3 Ki a máṣe mu ẹnikẹni yẹsẹ nipa wahalà wọnyi: nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ pe a ti yàn wa sinu rẹ̀. 4 Nitori nitõtọ nigbati awa wà lọdọ nyin, a ti nsọ fun nyin tẹlẹ pe, awa ó ri wahalà; gẹgẹ bi o si ti ṣẹ, ti ẹnyin si mọ̀. 5 Nitori eyi, nigbati ara mi kò gba a mọ́, mo si ranṣẹ ki emi ki o le mọ igbagbọ́ nyin ki oludanwò nì má bã ti dan nyin wo lọnakọna, ki lãlã wa si jẹ asan. 6 Ṣugbọn nisisiyi ti Timotiu ti ti ọdọ nyin wá sọdọ wa, ti o si ti mu ihinrere ti igbagbọ́ ati ifẹ nyin wá fun wa, ati pe ẹnyin nṣe iranti wa ni rere nigbagbogbo, ẹnyin si nfẹ gidigidi lati ri wa, bi awa pẹlu si ti nfẹ lati ri nyin: 7 Nitori eyi, ará, awa ni itunu lori nyin ninu gbogbo wahalà ati ipọnju wa nitori igbagbọ́ nyin: 8 Nitori awa yè nisisiyi, bi ẹnyin ba duro ṣinṣin ninu Oluwa. 9 Nitori ọpẹ́ kili awa le tún ma dá lọwọ Ọlọrun nitori nyin, fun gbogbo ayọ̀ ti awa nyọ̀ nitori nyin niwaju Ọlọrun wa; 10 Li ọsán ati li oru li awa ngbadura gidigidi pe, ki awa ki o le ri oju nyin, ki a si ṣe aṣepé eyiti o kù ninu igbagbọ́ nyin? 11 Njẹ ki Ọlọrun ati Baba wa tikararẹ, ati Jesu Kristi Oluwa wa, ṣe amọ̀na wa sọdọ nyin. 12 Ki Oluwa si mã mu nyin bisi i, ki ẹ si mã pọ̀ ninu ifẹ si ọmọnikeji nyin, ati si gbogbo enia, gẹgẹ bi awa ti nṣe si nyin: 13 Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.

1 Tessalonika 4

Ìgbé-Ayé Tí Ó Wu Ọlọrun

1 NJẸ li akotan, ará, awa mbẹ̀ nyin, awa si ngbà nyin niyanju ninu Jesu Oluwa, pe bi ẹnyin ti gbà lọwọ wa bi ẹnyin iba ti mã rìn, ti ẹnyin iba si mã wù Ọlọrun, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nrìn, ki ẹnyin le mã pọ̀ siwaju si i. 2 Nitori ẹnyin mọ̀ irú aṣẹ ti a ti pa fun nyin lati ọdọ Jesu Oluwa. 3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere: 4 Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá; 5 Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun: 6 Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu. 7 Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́. 8 Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu. 9 Ṣugbọn niti ifẹ awọn ará, ẹ kò tun fẹ ki ẹnikẹni kọwe si nyin: nitori a ti kọ́ ẹnyin tikaranyin lati ọdọ Ọlọrun wá lati mã fẹ ara nyin. 10 Nitõtọ ẹnyin si nṣe e si gbogbo awọn ará ti o wà ni gbogbo Makedonia: ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, pe ki ẹnyin ki o mã pọ̀ siwaju si i; 11 Ati pe ki ẹnyin ki o mã dù u gidigidi lati gbé jẹ, lati mã gbọ ti ara nyin, ki ẹ mã fi ọwọ́ nyin ṣiṣẹ, gẹgẹ bi awa ti paṣẹ fun nyin; 12 Ki ẹnyin ki o le mã rìn ìrin ẹ̀tọ́ si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ le má ṣe alaini ohunkohun.

Àkókò Tí Oluwa Yóo Dé

13 Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti. 14 Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀. 15 Nitori eyiyi li awa nwi fun nyin nipa ọ̀rọ Oluwa, pe awa ti o wà lãye, ti a si kù lẹhin de atiwá Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yio ṣaju awọn ti o sùn. 16 Nitori Oluwa tikararẹ̀ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ́ jinde: 17 Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lãye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹ̃li awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa. 18 Nitorina, ẹ mã fi ọ̀rọ wọnyi tu ara nyin ninu.

1 Tessalonika 5

Ẹ Múra Sílẹ̀ De Ìpadàbọ̀ Oluwa

1 ṢUGBỌN niti akokò ati ìgba wọnni, ará, ẹnyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si nyin, 2 Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru. 3 Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà. 4 Ṣugbọn ẹnyin, ará, kò si ninu òkunkun, ti ọjọ na yio fi de bá nyin bi olè. 5 Nitori gbogbo nyin ni ọmọ imọlẹ, ati ọmọ ọsán: awa kì iṣe ti oru, tabi ti òkunkun. 6 Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti nṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a mã ṣọna ki a si mã wa ni airekọja. 7 Nitori awọn ti nsùn, ama sùn li oru; ati awọn ti nmutipara, ama mutipara li oru. 8 Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsán, mã wà li airekọja, ki a mã gbé igbaiya igbagbọ́ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori. 9 Nitori Ọlọrun yàn wa ki iṣe si ibinu, ṣugbọn si ati ni igbala nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa, 10 Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀. 11 Nitorina ẹ mã gbà ara nyin niyanju, ki ẹ si mã fi ẹsẹ ara nyin mulẹ, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe.

Gbolohun Ìparí

12 Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin; 13 Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin. 14 Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia. 15 Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia. 16 Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. 17 Ẹ mã gbadura li aisimi. 18 Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. 19 Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. 20 Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. 21 Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. 22 Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi. 23 Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi. 24 Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e. 25 Ará, ẹ mã gbadura fun wa. 26 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí gbogbo awọn ará. 27 Mo fi Oluwa mu nyin bura pe, ki a ka iwe yi fun gbogbo awọn ará. 28 Ki ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu nyin. Amin.

2 Tessalonika 1

Ìkíni

1 PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa: 2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìdájọ́ Nígbà Tí Jesu Bá Dé

3 Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ; 4 Tobẹ̃ ti awa tikarawa nfi nyin ṣogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori sũru ati igbagbọ́ nyin ninu gbogbo inunibini ati wahalà nyin ti ẹnyin nfarada, 5 Eyiti iṣe àmi idajọ ododo Ọlọrun ti o daju, ki a le kà nyin yẹ fun ijọba Ọlọrun, nitori eyiti ẹnyin pẹlu ṣe njìya: 6 Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju, 7 Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀, 8 Ẹniti yio san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti nwọn kò si gbà ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́: 9 Awọn ẹniti yio jiya iparun ainipẹkun lati iwaju Oluwa wá, ati lati inu ogo agbara rẹ̀, 10 Nigbati o ba de lati jẹ ẹni ãyìn logo ninu awọn enia mimọ́ rẹ̀, ati ẹni iyanu ninu gbogbo awọn ti o gbagbọ́ (nitori a ti gbà ẹrí ti a jẹ fun nyin gbọ) li ọjọ na. 11 Nitori eyiti awa pẹlu ngbadura fun nyin nigbagbogbo, pe ki Ọlọrun wa ki o le kà nyin yẹ fun ìpe nyin, ki o le mu gbogbo ifẹ ohun rere ati iṣẹ igbagbọ́ ṣẹ ni agbara: 12 Ki a le yìn orukọ Jesu Oluwa wa logo ninu nyin, ati ẹnyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Oluwa.

2 Tessalonika 2

Ẹni Ibi Nnì

1 ṢUGBỌN awa mbẹ̀ nyin, ará, nitori ti wíwa Jesu Kristi Oluwa wa, ati ti ipejọ wa sọdọ rẹ̀, 2 Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de. 3 Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé; 4 Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on. 5 Ẹnyin kò ranti pe, nigbati mo wà lọdọ nyin, mo nsọ̀ nkan wọnyi fun nyin? 6 Ati nisisiyi ẹnyin mọ ohun ti o nṣe idena, ki a le ba fi i hàn li akokò rẹ̀. 7 Nitoripe ohun ijinlẹ ẹ̀ṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kìki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọ̀na kuro. 8 Nigbana li a ó si fi ẹ̀ṣẹ nì hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ̀ pa, ti yio si fi ifihan wíwa rẹ̀ sọ di asan: 9 Ani on, ẹniti wíwa rẹ̀ yio ri gẹgẹ bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo, ati àmi ati iṣẹ-iyanu eke, 10 Ati pẹlu itanjẹ aiṣododo gbogbo fun awọn ti nṣegbé; nitoriti nwọn kò gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là. 11 Ati nitori eyi, Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ́: 12 Ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo.

Ẹ̀yin tí Ọlọrun Yàn láti Gbà Là

13 Ṣugbọn iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, olufẹ nipa ti Oluwa, nitori lati àtetekọṣe li Ọlọrun ti yàn nyin si igbala ninu isọdimimọ́ Ẹmí ati igbagbọ́ otitọ: 14 Eyiti o ti pè nyin si nipa ihinrere wa, ki ẹnyin ki o le gbà ogo Jesu Kristi Oluwa wa. 15 Nitorina, ará, ẹ duro ṣinṣin, ki ẹ si dì ẹkọ́ wọnni mu ti a ti fi kọ́ nyin, yala nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe wa. 16 Njẹ ki Jesu Kristi Oluwa wa tikararẹ̀, ati Ọlọrun Baba wa, ẹniti o ti fẹ wa, ti o si ti fi itunu ainipẹkun ati ireti rere nipa ore-ọfẹ fun wa, 17 Ki o tù ọkan nyin ninu, ki o si fi ẹsẹ nyin mulẹ ninu iṣẹ ati ọrọ rere gbogbo.

2 Tessalonika 3

Ẹ Gbadura Fún Wa

1 LAKOTAN, ará, ẹ mã gbadura fun wa, ki ọ̀rọ Oluwa le mã sáre, ki o si jẹ ãyìn logo, ani gẹgẹ bi o ti ri lọdọ nyin: 2 Ati ki a le gbà wa lọwọ awọn aṣodi ati awọn enia buburu: nitoripe ki iṣe gbogbo enia li o gbagbọ́. 3 Ṣugbọn olododo li Oluwa, ẹniti yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, ti yio si pa nyin mọ́ kuro ninu ibi. 4 Awa si ni igbẹkẹle ninu Oluwa niti nyin, pe nkan wọnni ti a palaṣẹ fun nyin li ẹnyin nṣe ti ẹ o si mã ṣe. 5 Ki Oluwa ki o si mã tọ́ ọkan nyin sinu ifẹ Ọlọrun, ati sinu sũru Kristi.

Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Onímẹ̀ẹ́lẹ́

6 Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa. 7 Nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹnyin na farawe wa: nitori awa kò rin ségesège larin nyin; 8 Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn: 9 Kì iṣe pe awa kò li agbara, ṣugbọn awa nfi ara wa ṣe apẹrẹ fun nyin ki ẹnyin kì o le mã farawe wa. 10 Nitori nigbati awa tilẹ wà pẹlu nyin, eyi li awa palaṣẹ fun nyin, pe bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun. 11 Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri. 12 Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn. 13 Ṣugbọn ẹnyin, ará, ẹ máṣe ṣãrẹ̀ ni rere iṣe. 14 Bi ẹnikẹni kò ba si gbà ọ̀rọ wa gbọ́ nipa iwe yi, ẹ sami si oluwarẹ, ki ẹ má si ṣe ba a kẹgbẹ, ki oju ki o le tì i. 15 Sibẹ ẹ máṣe kà a si ọtá, ṣugbọn ẹ mã gbà a niyanju bi arakunrin.

Gbolohun Ìparí

16 Njẹ ki Oluwa alafia tikararẹ̀ mã fun nyin ni alafia nigbagbogbo lọna gbogbo. Ki Oluwa ki o pẹlu gbogbo nyin. 17 Ikíni emi Paulu lati ọwọ́ ara mi, eyiti iṣe àmi ninu gbogbo iwe; bẹ̃ni mo nkọwe. 18 Ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

1 Timotiu 1

1 PAULU, Aposteli Kristi Jesu, gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa, ati Kristi Jesu ireti wa; 2 Si Timotiu, ọmọ mi tõtọ ninu igbagbọ́: Ore-ọfẹ, ãnu, alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.

Ìkìlọ̀ nípa Ẹ̀kọ́ Èké

3 Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran, 4 Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi. 5 Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa. 6 Lati inu eyiti awọn ẹlomiran ti yapa kuro ti nwọn si ya sapakan si ọrọ asan; 7 Nwọn nfẹ ṣe olukọ ofin; òye ohun ti nwọn nwi kò yé wọn, tabi ti ohun ti nwọn ntẹnumọ́. 8 Ṣugbọn awa mọ̀ pe ofin dara, bi enia ba lò o bi ã ti ilo ofin; 9 Bi a ti mọ̀ eyi pe, a kò ṣe ofin fun olododo, bikoṣe fun awọn alailofin ati awọn alaigbọran, fun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ, fun awọn alaimọ́ ati awọn ẹlẹgan, fun awọn apa-baba ati awọn apa-iya, fun awọn apania, 10 Fun awọn àgbere, fun awọn ti nfi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, fun awọn ají-enia tà, fun awọn eke, fun awọn abura eke, ati bi ohun miran ba si wà ti o lodi si ẹkọ́ ti o yè koro, 11 Gẹgẹ bi ihinrere ti ogo Ọlọrun olubukún, ti a fi si itọju mi.

Ọpẹ́ fún Àánú Ọlọrun

12 Mo dupẹ lọwọ Ẹniti o fun mi li agbara, ani Kristi Jesu Oluwa wa, nitoriti o kà mi si olõtọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ̀; 13 Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ. 14 Ore-ọfẹ Oluwa wa si pọ̀ rekọja pẹlu igbagbọ́ ati ifẹ, ti mbẹ ninu Kristi Jesu. 15 Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki. 16 Ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri ãnu gbà, pe lara mi, bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rẹ̀ hàn bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ́ si ìye ainipẹkun nigba ikẹhin. 17 Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin. 18 Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere; 19 Mã ni igbagbọ́ ati ẹri-ọkàn rere; eyiti awọn ẹlomiran tanu kuro lọdọ wọn ti nwọn si rì ọkọ̀ igbagbọ́ wọn: 20 Ninu awọn ẹniti Himeneu ati Aleksanderu wà; awọn ti mo ti fi le Satani lọwọ, ki a le kọ́ wọn ki nwọn ki o má sọrọ-odi mọ́.

1 Timotiu 2

Ẹ̀kọ́ nípa Adura

1 NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia; 2 Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà. 3 Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa; 4 Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ. 5 Nitori Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu; 6 Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀; 7 Nitori eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, (otitọ li emi nsọ, emi kò ṣeke;) olukọ awọn Keferi ni igbagbọ́ ati otitọ. 8 Nitorina mo fẹ ki awọn ọkunrin mã gbadura nibi gbogbo, ki nwọn mã gbé ọwọ́ mimọ́ soke, li aibinu ati li aijiyan. 9 Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye, 10 Bikoṣe pẹlu iṣẹ́ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ ìwa-bi-Ọlọrun). 11 Jẹ ki obinrin ki o mã fi idakẹjẹ ati itẹriba gbogbo kọ́ ẹkọ́. 12 Ṣugbọn emi kò fi aṣẹ fun obinrin lati mã kọ́ni, tabi lati paṣẹ lori ọkunrin, bikoṣepe ki o dakẹjẹ. 13 Nitori Adamu li a kọ́ dá, lẹhin na, Efa. 14 A kò si tàn Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin na, nigbati a tàn a, o ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ. 15 Ṣugbọn a o gbà a là nipa ìbimọ rẹ̀, bi nwọn ba duro ninu igbagbọ́ ati ifẹ, ati ìwa mimọ́ pẹlu ìwa airekọja.

1 Timotiu 3

Irú Ẹni Tí Olùdarí Ìjọ Ní láti Jẹ́

1 OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ. 2 Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ. 3 Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo; 4 Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo; 5 (Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?) 6 Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu. 7 O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu.

Irú Ẹni Tí Diakoni Ní láti Jẹ́

8 Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro. 9 Ki nwọn mã di ohun ijinlẹ igbagbọ́ mu li ọkàn funfun. 10 Ki a si kọ́ wá idi awọn wọnyi daju pẹlu; nigbana ni ki a jẹ ki nwọn jẹ oyè diakoni, bi nwọn ba jẹ alailẹgan. 11 Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn obinrin lati ni iwa àgba, kì nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin bikoṣe alairekọja, olõtọ li ohun gbogbo. 12 Ki awọn diakoni jẹ ọkọ obinrin kan, ki nwọn ki o káwọ awọn ọmọ wọn ati ile ara wọn daradara. 13 Nitori awọn ti o lò oyè diakoni daradara rà ipo rere fun ara wọn, ati igboiya pupọ ni igbagbọ́ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.

Ohun Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀sìn Wa

14 Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si ọ, mo si nreti ati tọ̀ ọ wá ni lọ̃lọ̃. 15 Ṣugbọn bi mo ba pẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ bi o ti yẹ fun awọn enia lati mã huwa ninu ile Ọlọrun, ti iṣe ijọ Ọlọrun alãye, ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ. 16 Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.

1 Timotiu 4

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Àkókò Ìyapa ninu Ẹ̀sìn

1 ṢUGBỌN Ẹmí ntẹnumọ ọ pe, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, nwọn o mã fiyesi awọn ẹmí ti ntan-ni-jẹ, ati ẹkọ́ awọn ẹmí èṣu; 2 Nipa agabagebe awọn ti nṣeke, awọn ti ọkàn awọn tikarawọn dabi eyiti a fi irin gbigbona jó. 3 Awọn ti nda-ni-lẹkun ati gbeyawo, ti nwọn si npaṣẹ lati ka ẽwọ onjẹ ti Ọlọrun ti da fun itẹwọgba pẹlu ọpẹ awọn onigbagbọ ati awọn ti o mọ otitọ. 4 Nitori gbogbo ohun ti Ọlọrun dá li o dara, kò si ọkan ti o yẹ ki a kọ̀, bi a ba fi ọpẹ́ gbà a. 5 Nitori a fi ọ̀rọ Ọlọrun ati adura yà a si mimọ́.

Òjíṣẹ́ Rere Ti Kristi Jesu

6 Bi iwọ ba nrán awọn ará leti nkan wọnyi, iwọ o jẹ iranṣẹ rere ti Kristi Jesu, ti a nfi ọrọ igbagbọ́ ati ẹ̀kọ rere bọ́, eyiti iwọ ti ntẹle. 7 Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun. 8 Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀. 9 Otitọ ni ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà gbogbo. 10 Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́. 11 Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni. 12 Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́. 13 Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni. 14 Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba. 15 Mã fiyesi nkan wọnyi; fi ara rẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o le hàn gbangba fun gbogbo enia. 16 Mã ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ́ rẹ; mã duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ rẹ là.

1 Timotiu 5

Iṣẹ́ sí Àwọn tí ó Gbàgbọ́

1 MÁṢE ba alàgba wi, ṣugbọn ki o mã gba a niyanju bi baba; awọn ọdọmọkunrin bi arakunrin; 2 Awọn àgba obinrin bi iya; awọn ọdọmọbirin bi arabinrin ninu ìwa mimọ́. 3 Bọ̀wọ fun awọn opó ti iṣe opó nitõtọ. 4 Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun. 5 Njẹ ẹniti iṣe opó nitõtọ, ti o ṣe on nikan, a mã gbẹkẹle Ọlọrun, a si mã duro ninu ẹ̀bẹ ati ninu adura lọsán ati loru. 6 Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye. 7 Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o si mã palaṣẹ, ki nwọn ki o le wà lailẹgan. 8 Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá pèse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ̀, o ti sẹ́ igbagbọ́, o buru ju alaigbagbọ́ lọ. 9 Máṣe kọ orukọ ẹniti o ba din ni ọgọta ọdún silẹ bi opó, ti o ti jẹ obinrin ọkọ kan, 10 Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo. 11 Ṣugbọn kọ̀ awọn opo ti kò dagba: nitoripe nigbati nwọn ba ti ṣe ifẹkufẹ lodi si Kristi, nwọn a fẹ gbeyawo; 12 Nwọn a di ẹlẹbi, nitoriti nwọn ti kọ̀ igbagbọ́ wọn iṣaju silẹ. 13 Ati pẹlu nwọn nkọ́ lati ṣe ọlẹ, lati mã kiri lati ile de ile; ki iṣe ọlẹ nikan, ṣugbọn onisọkusọ ati olofòfo pẹlu, nwọn a ma sọ ohun ti kò yẹ. 14 Nitorina mo fẹ ki awọn opo ti kò dagba mã gbeyawo, ki nwọn mã bímọ, ki nwọn ki o mã ṣe alabojuto ile, ki nwọn ki o máṣe fi àye silẹ rara fun ọtá na lati sọ̀rọ ẹ̀gan. 15 Nitori awọn miran ti yipada kuro si ẹhin Satani. 16 Bi obinrin kan ti o gbagbọ́ ba ni awọn opó, ki o mã ràn wọn lọwọ, ki a má si di ẹrù le ijọ, ki nwọn ki o le mã ràn awọn ti iṣe opó nitõtọ lọwọ. 17 Awọn alàgba ti o ṣe akoso daradara ni ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe lãlã ni ọ̀rọ ati ni kikọni. 18 Nitoriti iwe-mimọ́ wipe, Iwọ kò gbọdọ dì malu ti ntẹ̀ ọkà li ẹnu. Ati pe, ọ̀ya alagbaṣe tọ si i. 19 Máṣe gbà ẹ̀sun si alàgba kan, bikoṣe lati ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta. 20 Ba awọn ti o ṣẹ̀ wi niwaju gbogbo enia, ki awọn iyokù pẹlu ki o le bẹ̀ru. 21 Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ati awọn angẹli ayanfẹ, ki iwọ ki o mã ṣakiyesi nkan wọnyi, laiṣe ojuṣãju, lai fi ègbè ṣe ohunkohun. 22 Máṣe fi ikanju gbe ọwọ́ le ẹnikẹni, bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ alabapin ninu ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹlomiran: pa ara rẹ mọ́ ni ìwa funfun. 23 Máṣe mã mu omi nikan, ṣugbọn mã lo waini diẹ nitori inu rẹ, ati nitori ailera rẹ igbakugba. 24 Ẹ̀ṣẹ awọn ẹlomiran a mã han gbangba, a mã lọ ṣãju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mã tẹle wọn. 25 Bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni iṣẹ rere wà ti nwọn hàn gbangba; awọn iru miran kò si le farasin.

1 Timotiu 6

1 KI gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ ìrú mã ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má bã sọrọ-odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ́ rẹ̀. 2 Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.

Ẹ̀kọ́ Burúkú ati Ọ̀rọ̀ Tòótọ́

3 Bi ẹnikẹni ba nkọ́ni li ẹkọ miran, ti kò si gba ọ̀rọ ti o ye kõro, ani ọ̀rọ Jesu Kristi Oluwa wa, ati ẹkọ́ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun. 4 O gberaga, kò mọ nkan kan, bikoṣe ifẹ iyan-jija ati ìja-ọ̀rọ ninu eyiti ilara, ìya, ọrọ buburu ati iro buburu ti iwá, 5 Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni. 6 Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni. 7 Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ. 8 Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn. 9 Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé. 10 Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.

Ìjà Rere ti Igbagbọ

11 Ṣugbọn iwọ enia Ọlọrun, sá fun nkan wọnyi; ki o si mã lepa ododo, ìwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ́, ifẹ, sũru, ìwa tutù. 12 Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀. 13 Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ti nsọ ohun gbogbo di ãye, ati niwaju Jesu Kristi, ẹni, niwaju Pontiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere, 14 Ki iwọ ki o pa ofin mọ́ li ailabawọn, li ailẹgan, titi di ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi: 15 Eyiti yio fihàn ni igba tirẹ̀, Ẹniti iṣe Olubukún ati Alagbara na kanṣoṣo, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa; 16 Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin. 17 Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo; 18 Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun; 19 Ki nwọn ki o mã tò iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wọn dè igba ti mbọ̀, ki nwọn ki o le di ìye tõtọ mu. 20 Timotiu, ṣọ ohun ni ti a fi si itọju rẹ, yà kuro ninu ọ̀rọ asan ati ijiyan ohun ti a nfi eke pè ni imọ; 21 Eyiti awọn ẹlomiran jẹwọ rẹ̀ ti nwọn si ṣina igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu rẹ. Amin.

2 Timotiu 1

1 PAULU, Aposteli Kristi Jesu nipa ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi ileri ìye ti mbẹ ninu Kristi Jesu, 2 Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.

Ìdúpẹ́ ati Ọ̀rọ̀ Ìwúrí

3 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, 4 T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn; 5 Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu. 6 Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ. 7 Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti ọkàn ti o yè kõro. 8 Nitorina máṣe tiju ẹrí Oluwa wa, tabi emi ondè rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alabapin ninu ipọnju ihinrere gẹgẹ bi agbara Ọlọrun; 9 Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye, 10 Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere, 11 Fun eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, ati olukọ. 12 Nitori idi eyiti emi ṣe njìya wọnyi pẹlu: ṣugbọn oju kò tì mi: nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì. 13 Dì apẹrẹ awọn ọ̀rọ ti o yè koro ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi mu, ninu igbagbọ́ ati ifẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. 14 Ohun rere nì ti a ti fi le ọ lọwọ, pa a mọ́ nipa Ẹmí Mimọ́ ti ngbe inu wa. 15 Eyi ni iwọ mọ̀, pe gbogbo awọn ti o wà ni Asia yipada kuro lẹhin mi; ninu awọn ẹniti Figellu ati Hermogene gbé wà. 16 Ki Oluwa ki o fi ãnu fun ile Onesiforu; nitoriti ima tù mi lara nigba pupọ̀, ẹ̀wọn mi kò si tì i loju: 17 Ṣugbọn nigbati o wà ni Romu, o fi ẹsọ̀ wá mi, o si ri mi. 18 Ki Oluwa ki o fifun u ki o le ri ãnu lọdọ Oluwa li ọjọ nì: iwọ tikararẹ sá mọ̀ dajudaju iye ohun ti o ṣe fun mi ni Efesu.

2 Timotiu 2

Ọmọ-Ogun Rere Ti Kristi Jesu

1 NITORINA, iwọ ọmọ mi, jẹ alagbara ninu ore-ọfẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. 2 Ati ohun wọnni ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi lati ọwọ ọ̀pọlọpọ ẹlẹri, awọn na ni ki iwọ fi le awọn olõtọ enia lọwọ, awọn ti yio le mã kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu. 3 Ṣe alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. 4 Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn. 5 Bi ẹnikẹni ba si njà, a kì dé e li ade, bikoṣepe o ba jà li aiṣe erú. 6 Àgbẹ ti o nṣe lãlã li o ni lati kọ́ mu ninu eso wọnni. 7 Gbà ohun ti emi nsọ rò; nitori Oluwa yio fun ọ li òye ninu ohun gbogbo. 8 Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi, 9 Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun. 10 Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun. 11 Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè: 12 Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa. 13 Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀. 14 Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ. 15 Ṣãpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yege, aṣiṣẹ́ ti kò ni lati tiju, ti o npín ọ̀rọ otitọ bi o ti yẹ. 16 Ṣugbọn yà kuro ninu ọ̀rọ asan, nitoriti nwọn ó mã lọ siwaju ninu aiwa-bi-Ọlọrun, 17 Ọrọ wọn yio si mã jẹ bi egbò kikẹ̀; ninu awọn ẹniti Himeneu ati Filetu wà; 18 Awọn ẹniti o ti ṣìna niti otitọ, ti nwipe ajinde ti kọja na; ti nwọn si mbì igbagbọ́ awọn miran ṣubu. 19 Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo. 20 Ṣugbọn ninu ile nla, kì iṣe kìki ohun elo wura ati ti fadaka nikan ni mbẹ nibẹ̀, ṣugbọn ti igi ati ti amọ̀ pẹlu; ati omiran si ọlá, ati omiran si ailọlá. 21 Bi ẹnikẹni ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ kuro ninu wọnyi, on ó jẹ ohun èlo si ọlá, ti a yà si ọ̀tọ, ti o si yẹ fun ìlo bãle, ti a si ti pèse silẹ si iṣẹ rere gbogbo. 22 Mã sá fun ifẹkufẹ ewe: si mã lepa ododo, igbagbọ́, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepè Oluwa lati inu ọkàn funfun wá. 23 Ṣugbọn ibẽre wère ati alaini ẹkọ́ ninu ni ki o kọ̀, bi o ti mọ̀ pe nwọn ama dá ìja silẹ. 24 Iranṣẹ Oluwa kò si gbọdọ jà; bikoṣe ki o jẹ ẹni pẹlẹ si enia gbogbo, ẹniti o le kọ́ni, onisũru, 25 Ẹniti yio mã kọ́ awọn aṣodi pẹlu iwa tutu; boya Ọlọrun le fun wọn ni ironupiwada si imọ otitọ; 26 Nwọn o si le sọji kuro ninu idẹkun Èṣu, awọn ti a ti dì ni igbekun lati ọwọ́ rẹ̀ wá si ifẹ rẹ̀.

2 Timotiu 3

Ìwà tí Àwọn Eniyan Yóo Máa Hù ní Ọjọ́ Ìkẹyìn

1 ṢUGBỌN eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yio de. 2 Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnú, agberaga, asọ̀rọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ́, 3 Alainifẹ, alaile darijini, abanijẹ́, alaile-kó-ra-wọnnijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere, 4 Onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ fãji jù olufẹ Ọlọrun lọ; 5 Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sẹ́ agbara rẹ̀: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu. 6 Nitori ninu irú eyi li awọn ti nrakò wọ̀ inu ile, ti nwọn si ndì awọn obinrin alailọgbọn ti a dì ẹ̀ṣẹ rù ni igbekùn, ti a si nfi onirũru ifẹkufẹ fà kiri, 7 Nwọn nfi igbagbogbo kẹ́kọ, nwọn kò si le de oju ìmọ otitọ. 8 Njẹ gẹgẹ bi Janesi ati Jamberi ti kọ oju ija si Mose, bẹ̃li awọn wọnyi kọ oju ija si otitọ: awọn enia ti inu wọn dibajẹ, awọn ẹni ìtanù niti ọran igbagbọ́. 9 Ṣugbọn nwọn kì yio lọ siwaju jù bẹ̃lọ: nitori wère wọn yio farahan fun gbogbo enia gẹgẹ bi tiwọn ti yọri si.

A Tún Kìlọ̀ fún Timotiu

10 Ṣugbọn iwọ ti mọ̀ ẹkọ́ mi, igbesi aiye mi, ipinnu, igbagbọ́, ipamọra, ifẹ́ni, sũru, 11 Inunibini, iyà; awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo faradà: Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn. 12 Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini. 13 Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ. 14 Ṣugbọn iwọ duro ninu nkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣa si, ki iwọ ki o si mọ̀ ọdọ ẹniti iwọ gbé kọ́ wọn; 15 Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. 16 Gbogbo iwe-mimọ́ ti o ni imísi Ọlọrun li o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibani-wi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo: 17 Ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.

2 Timotiu 4

1 NITORINA mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio ṣe idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ̀ ati ijọba rẹ̀, 2 Wasu ọ̀rọ na; ṣe aisimi li akokò ti o wọ̀, ati akokò ti kò wọ̀; baniwi, ṣe itọ́ni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹ̀kọ́ gbogbo. 3 Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. 4 Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan. 5 Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe. 6 Nitori a nfi mi rubọ nisisiyi, atilọ mi si sunmọ etile. 7 Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́: 8 Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìparí

9 Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá. 10 Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia. 11 Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ. 12 Mo rán Tikiku ni iṣẹ lọ si Efesu. 13 Aṣọ otutu ti mo fi silẹ ni Troa lọdọ Karpu, nigbati iwọ ba mbọ̀ mu u wá, ati iwe wọnni, pẹlupẹlu iwe-awọ wọnni. 14 Aleksanderu alagbẹdẹ bàba ṣe mi ni ibi pupọ̀: Oluwa yio san a fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: 15 Lọdọ ẹniti ki iwọ ki o mã ṣọra pẹlu; nitoriti o kọ oju ija si iwasu wa pupọ̀. 16 Li àtetekọ jẹ ẹjọ mi, kò si ẹniti o bá mi gba ẹjọ ro, ṣugbọn gbogbo enia li o kọ̀ mi silẹ: adura mi ni ki a máṣe kà a si wọn li ọrùn. 17 Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì. 18 Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbé mi de inu ijọba rẹ̀ ọrun: ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.

Ìdágbére

19 Kí Priskilla ati Akuila, ati ile Onesiforu. 20 Erastu wà ni Korinti: ṣugbọn mo fi Trofimu silẹ ni Miletu ninu aisan. 21 Sa ipa rẹ lati tete wá ṣaju ìgba otutù. Eubulu kí ọ, ati Pudeni, ati Linu, ati Klaudia, ati gbogbo awọn arakunrin. 22 Ki Oluwa ki o wà pẹlu ẹmí rẹ. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.

Titu 1

Ìkíni

1 PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun, 2 Ni ireti ìye ainipẹkun, ti Ọlọrun, Ẹniti kò le ṣèké, ti ṣe ileri ṣaju ipilẹṣẹ aiye; 3 Ṣugbọn ni akokò tirẹ̀ o fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn ninu iwasu, ti a fi le mi lọwọ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa; 4 Si Titu, ọmọ mi nitõtọ nipa igbagbọ́ ti iṣe ti gbogbo enia: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá ati Kristi Jesu Olugbala wa.

Iṣẹ́ Titu ní Kirete

5 Nitori idi eyi ni mo ṣe fi ọ silẹ ni Krete, ki iwọ ki o le ṣe eto ohun ti o kù, ki o si yan awọn alagba ni olukuluku ilu, bi mo ti paṣẹ fun ọ. 6 Bi ẹnikan ba ṣe alailẹgan, ọkọ aya kan, ti o ni ọmọ ti o gbagbọ́, ti a kò fi sùn fun wọbia, ti nwọn kò si jẹ alagidi. 7 Nitori o yẹ ki biṣopu jẹ alailẹgàn, bi iriju Ọlọrun; ki o má jẹ aṣe-tinu-ẹni, oninu-fùfu, ọmuti, aluni, olojukokoro; 8 Bikoṣe olufẹ alejò ṣiṣe, olufẹ awọn enia rere, alairekọja, olõtọ, ẹni mimọ́, ẹni iwọntunwọnsi; 9 Ti o ndì ọ̀rọ otitọ mu ṣinṣin eyiti iṣe gẹgẹ bi ẹ̀kọ́, ki on ki o le mã gbani-niyanju ninu ẹ̀kọ́ ti o yè kõro, ki o si le mã da awọn asọrọ-odi lẹbi. 10 Nitoripe ọpọlọpọ awọn alagídi, awọn asọ̀rọ asan, ati awọn ẹlẹtàn ni mbẹ, papa awọn ti ikọla: 11 Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́. 12 Ọkan ninu wọn, ani woli awọn tikarawọn, wipe, Eke ni awọn ará Krete nigbagbogbo, ẹranko buburu, ọlẹ alajẹki. 13 Otitọ li ẹrí yi. Nitorina bá wọn wi gidigidi, ki nwọn ki o le yè kõro ni igbagbọ́; 14 Ki nwọn máṣe fiyesi ìtan lasan ti awọn Ju, ati ofin awọn enia ti nwọn yipada kuro ninu otitọ. 15 Ohun gbogbo ni o mọ́ fun awọn ẹniti o mọ́, ṣugbọn fun awọn ti a sọ di ẹlẹgbin ati awọn alaigbagbọ́ kò si ohun ti o mọ́; ṣugbọn ati inu ati ẹ̀ri-ọkan wọn li a sọ di ẹgbin. 16 Nwọn jẹwọ pe nwọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ nwọn nsẹ́ ẹ, nwọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilari.

Titu 2

Ẹ̀kọ́ tí ó Yè Kooro

1 ṢUGBỌN iwọ mã sọ ohun ti o yẹ si ẹkọ́ ti o yè kõro: 2 Ki awọn àgba ọkunrin jẹ ẹni iwọntunwọnsin, ẹni-ọ̀wọ, alairekọja, ẹniti o yè kõro ni igbagbọ́, ni ifẹ, ni sũru. 3 Bẹ̃ gẹgẹ ni ki awọn agba obinrin jẹ ẹni-ọ̀wọ ni iwa, ki nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin, tabi ọmuti, bikoṣe olukọni ni ohun rere; 4 Ki nwọn ki o le tọ́ awọn ọdọmọbirin lati fẹran awọn ọkọ wọn, lati fẹran awọn ọmọ wọn, 5 Lati jẹ alairekọja, mimọ́, òṣiṣẹ́ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun ki o máṣe di isọ̀rọ-òdi si. 6 Bẹ̃ gẹgẹ ni ki o gbà awọn ọdọmọkunrin niyanju lati jẹ alairekọja. 7 Ninu ohun gbogbo mã fi ara rẹ hàn li apẹrẹ iṣẹ rere: ninu ẹkọ́ mã fi aiṣebajẹ hàn, ìwa àgba, 8 Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa. 9 Gbà awọn ọmọ-ọdọ niyanju lati mã tẹriba fun awọn oluwa wọn, ki nwọn ki o mã ṣe ohun ti o wu wọn ninu ohun gbogbo; ki nwọn ki o má gbó wọn lohùn; 10 Ki nwọn ki o máṣe irẹjẹ, ṣugbọn ki nwọn ki o mã fi iwa otitọ rere gbogbo han; ki nwọn ki o le mã ṣe ẹkọ́ Ọlọrun Olugbala wa li ọṣọ́ ninu ohun gbogbo. 11 Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan, 12 O nkọ́ wa pe, ki a sẹ́ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mã wà li airekọja, li ododo, ati ni ìwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi; 13 Ki a mã wo ọna fun ireti ti o ni ibukún ati ifarahan ogo Ọlọrun wa ti o tobi, ati ti Olugbala wa Jesu Kristi; 14 Ẹniti o fi ara rẹ̀ fun wa, ki on ki o le rà wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ gbogbo, ki o si le wẹ awọn enia kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ini on tíkararẹ awọn onitara iṣẹ rere. 15 Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o mã sọ, ki o si ma gbà-ni-niyanju, ki o si mã fi aṣẹ gbogbo ba-ni-wi. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ọ.

Titu 3

Ìlànà nípa Ìwà Tí Ó Dára

1 MÃ rán wọn leti lati mã tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati mã gbọ́ ti wọn, ati lati mã mura si iṣẹ rere gbogbo, 2 Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia. 3 Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa. 4 Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan, 5 Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́, 6 Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa; 7 Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun. 8 Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia. 9 Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn. 10 Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ; 11 Ki o mọ̀ pe irú ẹni bẹ̃ ti yapa, o si ṣẹ̀, o dá ara rẹ̀ lẹbi.

Gbolohun Ìparí

12 Nigbati mo ba rán Artema si ọ, tabi Tikiku, yara tọ̀ mi wá ni Nikopoli: nitori ibẹ ni mo ti pinnu lati lo akoko otutu. 13 Pese daradara fun Sena amofin ati Apollo li ọ̀na àjo wọn, ki ohunkohun maṣe kù wọn kù. 14 Ki awọn enia wa pẹlu si kọ́ lati mã ṣe iṣẹ rere fun ohun ti a kò le ṣe alaini, ki nwọn ki o má ba jẹ alaileso. 15 Gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi kí ọ. Kí awọn ti o fẹ wa ninu igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Filemoni 1

1 PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn, 2 Ati si Affia arabinrin wa, ati si Arkippu ọmọ-ogun ẹgbẹ wa, ati si ìjọ inu ile rẹ: 3 Ore-ọfẹ, ati alafia sí nyin, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìfẹ́ ati Igbagbọ Tí Filemoni Ní

4 Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, 5 Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́; 6 Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi. 7 Emi sá ni ayọ̀ pupọ ati itunu nitori ifẹ rẹ, nitoriti a tù ọkàn awọn enia mimọ́ lara lati ọwọ́ rẹ wá, arakunrin.

Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu

8 Nitorina, bi mo tilẹ ni igboiya pupọ̀ ninu Kristi lati paṣẹ ohun ti o yẹ fun ọ, 9 Ṣugbọn nitori ifẹ emi kuku bẹ̀bẹ, iru ẹni bi emi Paulu arugbo, ati nisisiyi ondè Kristi Jesu pẹlu. 10 Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu: 11 Nigbakan rí ẹniti o jẹ alailere fun ọ, ṣugbọn nisisiyi o lere fun ọ ati fun mi: 12 Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi: 13 Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere: 14 Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ. 15 Nitori boya idi rẹ̀ li eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ni i titi lai; 16 Kì iṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o jù ẹrú lọ, arakunrin olufẹ, papa fun mi, melomelo jubẹ̃lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa. 17 Nitorina bi iwọ ba kà mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gbà a bi emi tikarami. 18 Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn. 19 Emi Paulu li o fi ọwọ́ ara mi kọ ọ, emi ó san a pada: ki emi má sọ fun ọ, bi o ti jẹ mi nigbese ara rẹ pẹlu. 20 Nitõtọ, arakunrin, jẹ ki emi ki o ni ayọ̀ rẹ ninu Oluwa: tù ọkan mi lara ninu Kristi. 21 Bi mo ti ni igbẹkẹle ni igbọràn rẹ ni mo fi kọwe si ọ: nitori mo mọ̀ pe, iwọ ó tilẹ ṣe jù bi mo ti wi lọ. 22 Ati pẹlu, pese ìbuwọ̀ silẹ dè mi; nitori mo gbẹkẹle pe nipa adura nyin, a ó fi mi fun nyin.

Ìdágbére

23 Epafra, ondè ẹlẹgbẹ mi ninu Kristi Jesu kí ọ; 24 Marku, Aristarku, Dema, Luku, awọn olubaṣiṣẹ mi kí ọ pẹlu. 25 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.

Heberu 1

Ọlọrun Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀

1 ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni. 2 Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu; 3 Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;

Ọmọ Ọlọrun ju àwọn Angẹli lọ

4 O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ. 5 Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi? 6 Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u. 7 Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná. 8 Ṣugbọn niti Ọmọ li o wipe, Itẹ́ rẹ, Ọlọrun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ. 9 Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ. 10 Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ: 11 Nwọn ó ṣegbe; ṣugbọn iwọ ó wà sibẹ, gbogbo wọn ni yio si gbó bi ẹwu; 12 Ati bi aṣọ ni iwọ o si ká wọn, a o si pàrọ wọn: ṣugbọn bakanna ni iwọ, ọdún rẹ kì yio si pin. 13 Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? 14 Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?

Heberu 2

Ìgbàlà Ńlá

1 NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan. 2 Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́; 3 Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́; 4 Ọlọrun si nfi iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu, ati onirũru iṣẹ agbara, ati ẹ̀bun Ẹmí Mimọ́ bá wọn jẹri gẹgẹ bí ifẹ rẹ̀?

Ẹni tí Ó Ṣe Ọ̀nà Ìgbàlà

5 Nitoripe ki iṣe abẹ awọn angẹli li o fi aiye ti mbọ̀ ti awa nsọrọ rẹ̀ si. 6 Ṣugbọn ẹnikan sọ nibikan wipe, Kili enia ti o fi nṣe iranti rẹ̀, tabi ọmọ enia, ti o mbẹ̀ ẹ wò? 7 Iwọ dá a rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ; iwọ fi ogo ati ọlá dé e li ade, iwọ si fi i jẹ olori iṣẹ ọwọ́ rẹ: 8 Iwọ fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Nitori niti pe o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ kò kù ohun kan ti kò fi sabẹ rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi awa kò iti ri pe a fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀. 9 Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun. 10 Nitoripe o yẹ fun u, nitori ẹniti ohun gbogbo ṣe wà, ati nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ni mimu awọn ọmọ pupọ̀ wá sinu ogo, lati ṣe balogun igbala wọn li aṣepé nipa ìjiya. 11 Nitori ati ẹniti nsọni di mimọ́ ati awọn ti a nsọ di mimọ́, lati ọdọ ẹnikanṣoṣo ni gbogbo wọn: nitori eyiti ko ṣe tiju lati pè wọn ni arakunrin, 12 Wipe, Emi ó sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li ãrin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ. 13 Ati pẹlu, Emi o gbẹkẹ̀ mi le e. Ati pẹlu, Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Ọlọrun fifun mi. 14 Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu; 15 Ki o si le gbà gbogbo awọn ti o ti itori ibẹru iku wà labẹ ìde lọjọ aiye wọn gbogbo. 16 Nitoripe, nitõtọ ki iṣe awọn angẹli li o ṣe iranlọwọ fun, ṣugbọn irú-ọmọ Abrahamu li o ṣe iranlọwọ fun. 17 Nitorina o yẹ pe ninu ohun gbogbo ki o dabi awọn ará rẹ̀, ki o le jẹ alãnu ati olõtọ Olori Alufa ninu ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le ṣe etutu fun ẹ̀ṣẹ awọn enia. 18 Nitori niwọnbi on tikararẹ̀ ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndan wo lọwọ.

Heberu 3

Jesu Juu Mose Lọ

1 NITORINA ẹnyin ará mimọ́, alabapín ìpe ọ̀run, ẹ gbà ti Aposteli ati Olori Alufa ijẹwọ wa ro, ani Jesu; 2 Ẹniti o ṣe olõtọ si ẹniti o yàn a, bi Mose pẹlu ti ṣe ninu gbogbo ile rẹ̀. 3 Nitori a kà ọkunrin yi ni yiyẹ si ogo jù Mose lọ niwọn bi ẹniti o kọ́ ile ti li ọla jù ile lọ. 4 Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun. 5 Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin; 6 Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.

Ìsinmi fún Àwọn Eniyan Ọlọrun

7 Nitorina gẹgẹbi Ẹmí Mimọ́ ti wi, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, 8 Ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu, bi li ọjọ idanwò li aginjù: 9 Nibiti awọn baba nyin dán mi wò, nipa wiwadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi li ogoji ọdún. 10 Nitorina inu mi bajẹ si iran na, mo si wipe, Nigbagbogbo ni nwọn nṣìna li ọkàn wọn; nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi. 11 Bi mo ti bura ni ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi. 12 Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye. 13 Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ. 14 Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin; 15 Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu. 16 Nitori awọn tani bi nyin ninu nigbati nwọn gbọ́? Ki ha iṣe gbogbo awọn ti o ti ipasẹ Mose jade lati Egipti wá? 17 Awọn tali o si binu si fun ogoji ọdún? Ki ha iṣe si awọn ti o dẹṣẹ, okú awọn ti o sun li aginjù? 18 Awọn tali o si bura fun pe nwọn kì yio wọ̀ inu isimi on, bikoṣe fun awọn ti kò gbọran? 19 Awa si ri pe nwọn kò le wọ̀ inu rẹ̀ nitori aigbagbọ́.

Heberu 4

1 NITORINA, ẹ jẹ ki a bẹ̀ru, bi a ti fi ileri ati wọ̀ inu isimi rẹ̀ silẹ fun wa, ki ẹnikẹni ninu nyin ki o má bã dabi ẹnipe o ti kùna rẹ̀. 2 Nitoripe a ti wasu ihinrere fun wa gẹgẹ bi fun awọn na, ṣugbọn ọ̀rọ ti nwọn gbọ́ kò ṣe wọn ni ire, nitoriti kò dàpọ mọ́ igbagbọ́ ninu awọn ti o gbọ́ ọ. 3 Nitoripe awa ti o ti gbagbọ́ wọ̀ inu isimi gẹgẹ bi o ti wi, Bi mo ti bura ninu ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi: bi o tilẹ ti ṣe pe a ti pari iṣẹ wọnni lati ipilẹ aiye. 4 Nitori o ti sọ nibikan niti ọjọ keje bayi pe, Ọlọrun si simi ni ijọ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo. 5 Ati nihinyi ẹ̀wẹ pe, Nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi. 6 Nitorina bi o ti jẹ pe, o kù ki awọn kan wọ̀ inu rẹ̀, ati awọn ti a ti wasu ihinrere nã fun niṣãju kò wọ inu rẹ̀ nitori aigbọran: 7 Ẹ̀wẹ, o yan ọjọ kan, o wi ninu Iwe Dafidi pe, Loni, lẹhin igba pipẹ bẹ̃; bi a ti wi niṣãju, Loni bi ẹnyin ba gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le. 8 Nitori ibaṣepe Joṣua ti fun wọn ni isimi, on kì ba ti sọrọ nipa ọjọ miran lẹhinna. 9 Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun. 10 Nitoripe ẹniti o ba bọ́ sinu isimi rẹ̀, on pẹlu simi kuro ninu iṣẹ tirẹ̀, gẹgẹ bi Ọlọrun ti simi kuro ni tirẹ̀. 11 Nitorina ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ̀ inu isimi na, ki ẹnikẹni ki o má ba ṣubu nipa apẹrẹ aigbagbọ́ kanna. 12 Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn. 13 Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.

Jesu Olórí Alufaa Ńlá

14 Njẹ bi a ti ni Olori Alufa nla kan, ti o ti la awọn ọ̀run kọja lọ, Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a di ijẹwọ wa mu ṣinṣin. 15 Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ. 16 Nitorina ẹ jẹ ki a wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboiya, ki a le ri ãnu gbà, ki a si ri ore-ọfẹ lati mã rànnilọwọ ni akoko ti o wọ̀.

Heberu 5

1 NITORI olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mã mu ẹ̀bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ: 2 Ẹniti o le bá awọn alaimoye ati awọn ti o ti yapa kẹdun, nitori a fi ailera yi on na ká pẹlu. 3 Nitori idi eyi li o si ṣe yẹ, bi o ti nṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, bẹ̃ pẹlu ni ki o ṣe fun ara rẹ̀. 4 Kò si si ẹniti o gbà ọlá yi fun ara rẹ̀, bikoṣe ẹniti a pè lati ọdọ Ọlọrun wá, gẹgẹ bi a ti pè Aaroni. 5 Bẹ̃ni Kristi pẹlu kò si ṣe ara rẹ̀ logo lati jẹ́ Olori Alufa; bikoṣe ẹniti o wi fun u pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. 6 Bi o ti wi pẹlu nibomiran pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. 7 Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀, 8 Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya; 9 Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀: 10 Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.

Ìkìlọ̀ nípa Àwọn tí Ó Kúrò ninu Ẹ̀sìn Igbagbọ

11 Niti ẹniti awa ni ohun pupọ̀ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitoripe ẹ yigbì ni gbigbọ́. 12 Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile. 13 Nitori olukuluku ẹniti nmu wàra jẹ́ alailoye ọ̀rọ ododo: nitori ọmọ-ọwọ ni. 14 Ṣugbọn onjẹ lile ni fun awọn ti o dagba, awọn ẹni nipa ìriri, ti nwọn nlò ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ sarin rere ati buburu.

Heberu 6

1 NITORINA ki a fi ipilẹṣẹ ẹkọ́ Kristi silẹ, ki a lọ si pipé; li aitún fi ipilẹ ironupiwada kuro ninu okú iṣẹ lelẹ, ati ti igbagbọ́ sipa ti Ọlọrun, 2 Ati ti ẹkọ́ ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun. 3 Eyi li awa ó si ṣe, bi Ọlọrun fẹ. 4 Nitori awọn ti a ti là loju lẹ̃kan, ti nwọn si ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, ti nwọn si ti di alabapin Ẹmí Mimọ́, 5 Ti nwọn si ti tọ́ ọ̀rọ rere Ọlọrun wò, ati agbara aiye ti mbọ̀, 6 Ti nwọn si ti ṣubu kuro, ko le ṣe iṣe lati sọ wọn di ọtun si ironupiwada, nitori nwọn tún kàn Ọmọ Ọlọrun mọ agbelebu si ara wọn li ọtun, nwọn si dojutì i ni gbangba. 7 Nitori ilẹ ti o fi omi ojò ti nrọ̀ sori rẹ̀ nigbagbogbo mu, ti o si nhù ewebẹ ti o dara fun awọn ti a nti itori wọn ro o pẹlu, ngbà ibukún lọwọ Ọlọrun. 8 Ṣugbọn eyiti o nhù ẹgún ati oṣuṣu, a kọ̀ ọ, kò si jìna si egún; opin eyiti yio jẹ fun ijona. 9 Ṣugbọn, olufẹ, awa ni igbagbọ ohun ti o dara jù bẹ̃ lọ niti nyin, ati ohun ti o faramọ igbala, bi awa tilẹ nsọ bayi. 10 Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe. 11 Awa si fẹ ki olukuluku nyin ki o mã fi irú aisimi kanna hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin: 12 Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri.

Ìlérí Ọlọrun Tí Ó Dájú

13 Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ̀ bura, wipe, 14 Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i. 15 Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà. 16 Nitori enia a mã fi ẹniti o pọjù wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹ ọ̀rọ. 17 Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn. 18 Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu: 19 Eyiti awa ni bi idakọ̀ro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin, ti o si wọ̀ inu ile lọ lẹhin aṣọ ikele; 20 Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.

Heberu 7

Irú Alufaa tí Mẹlikisẹdẹki Jẹ́

1 NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u; 2 Ẹniti Abrahamu si pin idamẹwa ohun gbogbo fun; li ọna ekini ni itumọ rẹ̀ ọba ododo, ati lẹhinna pẹlu ọba Salemu, ti iṣe ọba alafia; 3 Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi. 4 Njẹ ẹ gbà a rò bi ọkunrin yi ti pọ̀ to, ẹniti Abrahamu baba nla fi idamẹwa ninu awọn aṣayan ikogun fun. 5 Ati nitõtọ awọn ti iṣe ọmọ Lefi, ti o gbà oyè alufa, nwọn ni aṣẹ lati mã gbà idamẹwa lọwọ awọn enia gẹgẹ bi ofin, eyini ni, lọwọ awọn arakunrin wọn, bi o tilẹ ti jẹ pe, nwọn ti inu Abrahamu jade. 6 Ṣugbọn on ẹniti a kò tilẹ pitan iran rẹ̀ lati ọdọ wọn wá, ti gbà idamẹwa lọwọ Abrahamu, o si ti sure fun ẹniti o gbà ileri. 7 Ati li aisijiyan rara ẹniti kò to ẹni li ã sure fun lati ọdọ ẹniti o jù ni. 8 Ati nihin, awọn ẹni kikú gbà idamẹwa; ṣugbọn nibẹ̀, ẹniti a jẹri rẹ̀ pe o mbẹ lãye. 9 Ati bi a ti le wi, Lefi papa ti ngbà idamẹwa, ti san idamẹwa nipasẹ Abrahamu. 10 Nitori o sá si mbẹ ni inu baba rẹ̀, nigbati Melkisedeki pade rẹ̀. 11 Njẹ ibaṣepe pipé mbẹ nipa oyè alufa Lefi, (nitoripe labẹ rẹ̀ li awọn enia gbà ofin), kili o si tún kù mọ́ ti alufa miran iba fi dide nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti a kò si wipe nipa ẹsẹ Aaroni? 12 Nitoripe bi a ti pàrọ oyè alufa, a kò si le ṣai pàrọ ofin. 13 Nitori ẹniti a nsọ̀rọ nkan wọnyi nipa rẹ̀ jẹ ẹ̀ya miran, lati inu eyiti ẹnikẹni koi jọsin ri nibi pẹpẹ. 14 Nitori o han gbangba pe lati inu ẹ̀ya Juda ni Oluwa wa ti dide; nipa ẹ̀ya ti Mose kò sọ ohunkohun niti awọn alufa.

Oyè Alufaa Titun, Gẹ́gẹ́ Bíi ti Mẹlikisẹdẹki

15 O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki, 16 Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin. 17 Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. 18 Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀. 19 (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun. 20 Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni. 21 (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:) 22 Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù. 23 Ati nitõtọ awọn pupọ̀ li a ti fi jẹ alufa, nitori nwọn kò le wà titi nitori ikú: 24 Ṣugbọn on, nitoriti o wà titi lai, o ni oyè alufa ti a kò le rọ̀ nipò. 25 Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn. 26 Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ; 27 Ẹniti kò ni lati mã kọ́ rubọ lojojumọ, bi awọn olori alufa wọnni, fun ẹ̀ṣẹ ti ara rẹ̀ na, ati lẹhinna fun ti awọn enia: nitori eyi li o ti ṣe lẹ̃kanṣoṣo, nigbati o fi ara rẹ̀ rubọ. 28 Nitoripe ofin a mã fi awọn enia ti o ni ailera jẹ olori alufa; ṣugbọn ọ̀rọ ti ibura, ti a ṣe lẹhin ofin, o fi Ọmọ jẹ, ẹniti a sọ di pipé titi lai.

Heberu 8

Olórí Alufaa ti Majẹmu Titun

1 NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun: 2 Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia. 3 Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ. 4 Nisisiyi ibaṣepe o mbẹ li aiye, on kì bá tilẹ jẹ alufa, nitori awọn ti nfi ẹbun rubọ gẹgẹ bi ofin mbẹ: 5 Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke. 6 Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹ̃ lọ. 7 Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji. 8 Nitoriti o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun. 9 Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi. 10 Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi: 11 Olukuluku kì yio si mã kọ́ ara ilu rẹ̀ ati olukuluku arakunrin rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ̀ mi, lati kekere de àgba. 12 Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́. 13 Li eyi ti o wipe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai. Ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan.

Heberu 9

Ilé Ìsìn Ti Ayé ati Ti Ọ̀run

1 NJẸ majẹmu iṣaju papa pẹlu ní ìlana ìsin, ati ibi mimọ́ ti aiye yi. 2 Nitoripe a pa agọ́ kan; eyi ti iṣaju ninu eyi ti ọpá fitila, ati tabili, ati akara ifihàn gbé wà, eyiti a npè ni ibi mimọ́. 3 Ati lẹhin aṣọ ikele keji, on ni agọ́ ti a npè ni ibi mimọ julọ; 4 Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu; 5 Ati lori rẹ̀ ni awọn kerubu ogo ti o ṣijibo ìtẹ́ ãnu; eyiti a kò le sọrọ rẹ̀ nisisiyi lọkọ̃kan. 6 Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin. 7 Ṣugbọn sinu ekeji ni olori alufa nikan imã lọ lẹ̃kanṣoṣo li ọdún, kì iṣe li aisi ẹ̀jẹ, ti on fi rubọ fun ara rẹ̀ na, ati fun ìṣina awọn enia: 8 Ẹmí Mimọ́ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọ̀na ibi mimọ́ silẹ niwọn igbati agọ́ ekini ba duro. 9 Eyiti iṣe apẹrẹ fun igba isisiyi gẹgẹ bi eyiti a nmu ẹ̀bun ati ẹbọ wá, ti kò le mu olusin di pipé niti ohun ti ẹri-ọkàn, 10 Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe. 11 Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi. 12 Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa. 13 Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara, 14 Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye? 15 Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà. 16 Nitori nibiti iwe-ogún ba gbé wà, ikú ẹniti o ṣe e kò le ṣe aisi pẹlu. 17 Nitori iwe-ogún li agbara lẹhin igbati enia ba kú: nitori kò li agbara rara nigbati ẹniti o ṣe e ba mbẹ lãye. 18 Nitorina li a kò ṣe yà majẹmu iṣaju papa si mimọ́ laisi ẹ̀jẹ. 19 Nitori nigbati Mose ti sọ gbogbo aṣẹ fun gbogbo awọn enia gẹgẹ bi ofin, o mu ẹ̀jẹ ọmọ malu ati ti ewurẹ, pẹlu omi, ati owu ododó, ati ewe hissopu, o si fi wọ́n ati iwe pãpã ati gbogbo enia, 20 Wipe, Eyi li ẹ̀jẹ majẹmu ti Ọlọrun palaṣẹ fun nyin. 21 Bẹ gẹgẹ li o si fi ẹ̀jẹ wọ́n agọ́, ati gbogbo ohun èlo ìsin. 22 O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji.

Ẹbọ tí Jesu Rú Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù

23 Nitorina a kò le ṣai fi iwọnyi wẹ̀ awọn apẹrẹ ohun ti mbẹ lọrun mọ́; ṣugbọn o yẹ ki a fi ẹbọ ti o san ju iwọnyi lọ wẹ̀ awọn ohun ọrun pãpã mọ́. 24 Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa: 25 Kì si iṣe pe ki o le mã fi ara rẹ̀ rubọ nigbakugba, bi olori alufa ti ima wọ̀ inu ibi mimọ́ lọ li ọdọ̃dún ti on ti ẹ̀jẹ ti ki ṣe tirẹ̀; 26 Bi bẹ̃kọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹ̃kanṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀. 27 Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ: 28 Bẹ̃ni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lẹ̃kanṣoṣo lati ru ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ, yio farahan nigbakeji laisi ẹ̀ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rẹ̀ fun igbala.

Heberu 10

1 NITORI ofin bi o ti ni ojiji awọn ohun rere ti mbọ̀ laijẹ aworan pãpã awọn nkan na, nwọn kò le fi ẹbọ kanna ti nwọn nru nigbagbogbo li ọdọ̃dún mu awọn ti nwá sibẹ̀ di pipé. 2 Bikoṣe bẹ̃, a kì bá ha ti dẹkun ati mã rú wọn, nitori awọn ti nsìn kì bá tí ni ìmọ ẹ̀ṣẹ, nigbati a ba ti wẹ wọn mọ lẹ̃kanṣoṣo. 3 Ṣugbọn ninu ẹbọ wọnni ni a nṣe iranti ẹ̀ṣẹ li ọdọdún. 4 Nitori ko ṣe iṣe fun ẹ̀jẹ akọ malu ati ti ewurẹ lati mu ẹ̀ṣẹ kuro. 5 Nitorina nigbati o wá si aiye, o wipe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ṣugbọn ara ni iwọ ti pèse fun mi: 6 Ẹbọ sisun ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ ni iwọ kò ni inu didùn si. 7 Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i (ninu iwe-kiká nì li a gbé kọ ọ nipa ti emi) Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. 8 Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin). 9 Nigbana ni o wipe, Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. O mu ti iṣaju kuro, ki o le fi idi ekeji mulẹ. 10 Nipa ifẹ na li a ti sọ wa di mimọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ̃kanṣoṣo. 11 Ati olukuluku alufa si nduro li ojojumọ́ o nṣe ìsin, o si nṣe ẹbọ kanna nigbakugba, ti kò le mu ẹ̀ṣẹ kuro lai: 12 Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; 13 Lati igbà na lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọtá rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀. 14 Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai. 15 Ẹmí Mimọ́ si njẹri fun wa pẹlu: nitori lẹhin ti o ti wipe, 16 Eyi ni majẹmu ti emi ó ba wọn dá lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si wọn li ọkàn, inu wọn pẹlu li emi o si kọ wọn si; 17 Ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́. 18 Ṣugbọn nibiti imukuro iwọnyi ba gbé wà, irubọ fun ẹ̀ṣẹ kò si mọ́.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú ati Ìkìlọ̀

19 Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu, 20 Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀; 21 Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun; 22 Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù. 23 Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;) 24 Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere: 25 Ki a má mã kọ ipejọpọ̀ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mã gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile. 26 Nitori bi awa ba mọ̃mọ̀ dẹṣẹ lẹhin igbati awa ba ti gbà ìmọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ mọ́, 27 Bikoṣe ireti idajọ ti o ba ni lẹrù, ati ti ibinu ti o muná, ti yio pa awọn ọtá run. 28 Ẹnikẹni ti o ba gàn ofin Mose, o kú li aisi ãnu nipa ẹri ẹni meji tabi mẹta: 29 Melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ̀ ni ìya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimọ́ si ohun aimọ́, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ. 30 Nitori awa mọ̀ ẹniti o wipe, Ẹsan ni ti emi, Oluwa wipe, Emi o gbẹsan. Ati pẹlu, Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀. 31 Ohun ẹ̀ru ni lati ṣubu si ọwọ́ Ọlọrun alãye. 32 Ṣugbọn ẹ ranti ọjọ iṣaju, ninu eyiti, nigbati a ti ṣí nyin loju, ẹ fi ara da wahala ijiya nla; 33 Lapakan, nigbati a sọ nyin di iran wiwo nipa ẹ̀gan ati ipọnju; ati lapakan, nigbati ẹnyin di ẹgbẹ awọn ti a ṣe bẹ̃ si. 34 Nitori ẹnyin bá awọn ti o wà ninu ìde kẹdun, ẹ si fi ayọ̀ gbà ìkolọ ẹrù nyin, nitori ẹnyin mọ̀ ninu ara nyin pe, ẹ ni ọrọ̀ ti o wà titi, ti o si dara ju bẹ̃ lọ li ọ̀run. 35 Nitorina ẹ máṣe gbe igboiya nyin sọnu, eyiti o ni ère nla. 36 Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na. 37 Nitori niwọn igba diẹ si i, Ẹni nã ti mbọ̀ yio de, kì yio si jafara. 38 Ṣugbọn olododo ni yio yè nipa igbagbọ́: ṣugbọn bi o ba fà sẹhin, ọkàn mi kò ni inu didùn si i. 39 Ṣugbọn awa kò si ninu awọn ti nfà sẹhin sinu egbé; bikoṣe ninu awọn ti o gbagbọ́ si igbala ọkàn.

Heberu 11

Igbagbọ

1 NJẸ igbagbọ́ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri. 2 Nitori ninu rẹ̀ li awọn alàgba ti ni ẹri rere. 3 Nipa igbagbọ́ li a mọ̀ pe a ti da aiye nipa ọ̀rọ Ọlọrun; nitorina ki iṣe ohun ti o hàn li a fi dá ohun ti a nri. 4 Nipa igbagbọ́ ni Abeli ru ẹbọ si Ọlọrun ti o san ju ti Kaini lọ, nipa eyiti a jẹri rẹ̀ pe olododo ni, Ọlọrun si njẹri ẹ̀bun rẹ̀: ati nipa rẹ̀ na, bi o ti kú ni, o nfọhùn sibẹ̀. 5 Nipa igbagbọ́ li a ṣí Enoku nipò pada ki o máṣe ri ikú; a kò si ri i, nitoriti Ọlọrun ṣí i nipò pada: nitori ṣaju iṣipopada rẹ̀, a jẹrí yi si i pe o wù Ọlọrun. 6 Ṣugbọn li aisi igbagbọ́ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ̀ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ́ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a. 7 Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́. 8 Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè. 9 Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀: 10 Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́. 11 Nipa igbagbọ́ ni Sara tikararẹ̀ pẹlu fi ni agbara lati lóyun, nigbati o kọja ìgba rẹ̀, nitoriti o kà ẹniti o ṣe ileri si olõtọ. 12 Nitorina li ọ̀pọlọpọ ṣe ti ara ẹnikan jade, ani ara ẹniti o dabi okú, ọ̀pọ bi irawọ oju ọrun li ọ̀pọlọpọ, ati bi iyanrin eti okun li ainiye. 13 Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbọ́, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti nwọn ri wọn li òkere rere, ti nwọn si gbá wọn mú, ti nwọn si jẹwọ pe alejò ati atipò li awọn lori ilẹ aiye. 14 Nitoripe awọn ti o nsọ irú ohun bẹ̃, fihan gbangba pe, nwọn nṣe afẹri ilu kan ti iṣe tiwọn. 15 Ati nitõtọ, ibaṣepe nwọn fi ilu tí nwọn ti jade wa si ọkàn, nwọn iba ti ri aye lati pada. 16 Ṣugbọn nisisiyi nwọn nfẹ ilu kan ti o dara jù bẹ̃ lọ, eyini ni ti ọ̀run: nitorina oju wọn kò ti Ọlọrun, pe ki a mã pe On ni Ọlọrun wọn; nitoriti o ti pèse ilu kan silẹ fun wọn. 17 Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a dán a wò, fi Isaaki rubọ: ẹniti o si ti fi ayọ̀ gbà ileri wọnni fi ọmọ-bíbi rẹ̀ kanṣoṣo rubọ. 18 Niti ẹniti a wipe, Ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ: 19 O si pari rẹ̀ si pe Ọlọrun tilẹ le gbe e dide, ani kuro ninu oku, ati ibiti o ti gbà a pada pẹlu ni apẹrẹ. 20 Nipa igbagbọ́ ni Isaaki sure fun Jakọbu ati Esau niti ohun ti mbọ̀. 21 Nipa igbagbọ́ ni Jakọbu, nigbati o nkú lọ, o súre fun awọn ọmọ Josefu ni ọ̀kọ̃kan; o si tẹriba, o simi le ori ọpá rẹ̀. 22 Nipa igbagbọ́ ni Josefu, nigbati o nkú lọ, o ranti ìjadelọ awọn ọmọ Israeli; o si paṣẹ niti awọn egungun rẹ̀. 23 Nipa igbagbọ́ ni awọn obi Mose pa a mọ́ fun oṣu mẹta nigbati a bí i, nitoriti nwọn ri i ni arẹwa ọmọ; nwọn kò si bẹ̀ru aṣẹ ọba. 24 Nipa igbagbọ́ ni Mose, nigbati o dàgba, o kọ̀ ki a mã pè on li ọmọ ọmọbinrin Farao; 25 O kuku yàn ati mã bá awọn enia Ọlọrun jìya, jù ati jẹ fãji ẹ̀ṣẹ fun igba diẹ; 26 O kà ẹ̀gan Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitoriti o nwo ère na. 27 Nipa igbagbọ́ li o kọ̀ Egipti silẹ li aibẹ̀ru ibinu ọba: nitoriti o duro ṣinṣin bi ẹniti o nri ẹni airi. 28 Nipa igbagbọ́ li o dá ase irekọja silẹ, ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ, ki ẹniti npa awọn akọbi ọmọ ki o má bã fi ọwọ́ kàn wọn. 29 Nipa igbagbọ́ ni nwọn là okun pupa kọja bi ẹnipe ni iyangbẹ ilẹ: ti awọn ara Egipti danwò, ti nwọn si rì. 30 Nipa igbagbọ́ li awọn odi Jeriko wó lulẹ, lẹhin igbati a yi wọn ká ni ijọ meje. 31 Nipa igbagbọ́ ni Rahabu panṣaga kò ṣegbé pẹlu awọn ti kò gbọran, nigbati o tẹwọgbà awọn amí li alafia. 32 Ewo li emi o si tun mã wi si i? nitoripe ãyè kò ni tó fun mi lati sọ ti Gideoni, ati Baraku, ati Samsoni, ati Jefta; ti Dafidi, ati Samueli, ati ti awọn woli: 33 Awọn ẹni nipasẹ igbagbọ́ ti nwọn ṣẹgun ilẹ ọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn dí awọn kiniun li ẹnu, 34 Ti nwọn pa agbara iná, ti nwọn bọ́ lọwọ oju-idà, ti a sọ di alagbara ninu ailera, ti nwọn di akọni ni ìja, nwọn lé ogun awọn àjeji sá. 35 Awọn obinrin ri okú wọn gbà nipa ajinde: a si dá awọn ẹlomiran lóro, nwọn kọ̀ lati gbà ìdasilẹ; ki nwọn ki o le ri ajinde ti o dara jù gbà: 36 Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti ìnà, ati ju bẹ̃ lọ ti ìde ati ti tubu: 37 A sọ wọn li okuta, a fi ayùn rẹ́ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro; 38 Awọn ẹniti aiye kò yẹ fun: nwọn nkiri ninu aṣálẹ, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ. 39 Gbogbo awọn wọnyi ti a jẹri rere sí nipa igbagbọ́, nwọn kò si ri ileri na gbà: 40 Nitori Ọlọrun ti pèse ohun ti o dara jù silẹ fun wa, pe li aisi wa, ki a má ṣe wọn pé.

Heberu 12

Ìtọ́ni ti Oluwa

1 NITORINA bi a ti fi awọsanmọ ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri yí wa ká, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹ̀ṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa, ki a si mã fi sũru sure ije ti a gbé ka iwaju wa, 2 Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun. 3 Sá ro ti ẹniti o farada irú isọrọ-odì yi lati ọdọ awọn ẹlẹṣẹ si ara rẹ̀, ki ẹ má ba rẹwẹsi ni ọkàn nyin, ki ãrẹ si mu nyin. 4 Ẹnyin kò ìtĩ kọ oju ija si ẹ̀ṣẹ titi de ẹ̀jẹ ni ijakadi nyin. 5 Ẹnyin si ti gbagbé ọ̀rọ iyanju ti mba nyin sọ bi ọmọ pe, Ọmọ mi, má ṣe alainani ibawi Oluwa, ki o má si ṣe rẹwẹsi nigbati a ba nti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wi: 6 Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà. 7 Ẹ mã mu suru labẹ ibawi: Ọlọrun mba nyin lo bi ọmọ ni; nitoripe ọmọ wo ni mbẹ ti baba ki ibawi? 8 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wà li aisi ibawi, ninu eyiti gbogbo enia ti jẹ alabapin, njẹ ọmọ àle ni nyin, ẹ kì isi iṣe ọmọ. 9 Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́ wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba awọn ẹmí ki a si yè? 10 Nitori nwọn tọ́ wa fun ọjọ diẹ bi o ba ti dara loju wọn; ṣugbọn on fun ère wa, ki awa ki o le ṣe alabapin ìwa mimọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo. 12 Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera; 13 Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san.

Ìkìlọ̀ Kí Eniyan má Kọ Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun

14 Ẹ mã lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ́, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa: 15 Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe kùna ore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbòngbo ikorò kan ki o má ba hù soke ki o si yọ nyin lẹnu, ọ̀pọlọpọ a si ti ipa rẹ̀ di aimọ́; 16 Ki o má bã si àgbere kan tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Esau, ẹniti o ti itori òkele onjẹ kan tà ogún ibí rẹ̀. 17 Nitori ẹnyin mọ̀ pe lẹhinna ní ani nigbati o fẹ lati jogun ibukun na, a kọ̀ ọ (nitori kò ri aye ironupiwada) bi o tilẹ ti fi omije wá a gidigidi. 18 Nitori ẹnyin kò wá si òke, ti a le fi ọwọ kàn, ati si iná ti njó, ati si iṣúdùdu ati òkunkun, ati iji, 19 Ati iró ipè, ati ohùn ọ̀rọ, eyiti awọn ti o gbọ́ bẹ̀bẹ pe, ki a máṣe sọ ọ̀rọ si i fun wọn mọ́: 20 Nitoripe ara wọn kò le gbà ohun ti o palaṣẹ, Bi o tilẹ jẹ ẹranko li o farakan òke na, a o sọ ọ li okuta, tabi a o gún u li ọ̀kọ pa. 21 Iran na si lẹrù tobẹ̃, ti Mose wipe, ẹ̀ru bà mi gidigidi mo si warìri. 22 Ṣugbọn ẹnyin wá si òke Sioni, ati si ilu Ọlọrun alãye, si Jerusalemu ti ọ̀run, ati si ẹgbẹ awọn angẹli ainiye, 23 Si ajọ nla ati ìjọ akọbi ti a ti kọ orukọ wọn li ọ̀run, ati sọdọ Ọlọrun onidajọ gbogbo enia, ati sọdọ awọn ẹmí olõtọ enia ti a ṣe li aṣepé, 24 Ati sọdọ Jesu alarina majẹmu titun, ati si ibi ẹ̀jẹ ibuwọ́n nì, ti nsọ̀rọ ohun ti o dara jù ti Abeli lọ. 25 Kiyesi i, ki ẹ máṣe kọ̀ ẹniti nkilọ. Nitori bi awọn wọnni kò ba bọ́ nigbati nwọn kọ̀ ẹniti nkilọ li aiye, melomelo li awa kì yio bọ́ awa ti o pẹhinda si ẹniti nkilọ lati ọrun wá: 26 Ohùn ẹniti o mì aiye nigbana: ṣugbọn nisisiyi o ti ṣe ileri, wipe, Lẹ̃kan si i emi kì yio mì kìki aiye nikan, ṣugbọn ọrun pẹlu. 27 Ati ọ̀rọ yi, Lẹ̃kan si i, itumọ rẹ̀ ni mimu awọn ohun wọnni ti a nmì kuro, bi ohun ti a ti da, ki awọn ohun wọnni ti a kò le mì le wà sibẹ. 28 Nitorina bi awa ti ngbà ilẹ ọba ti a kò le mì, ẹ jẹ ki a ni ore-ọfẹ nipa eyiti awa le mã sin Ọlọrun ni itẹwọgbà pẹlu ọ̀wọ ati ibẹru rẹ̀. 29 Nitoripe Ọlọrun wa, iná ti ijonirun ni.

Heberu 13

Ìsìn Tí Ó Wu Ọlọrun

1 KI ifẹ ará ki o wà titi. 2 Ẹ máṣe gbagbé lati mã ṣe alejò; nitoripe nipa bẹ̃ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejò laimọ̀. 3 Ẹ mã ranti awọn onde bi ẹniti a dè pẹlu wọn, ati awọn ti a npọn loju bi ẹnyin tikaranyin pẹlu ti mbẹ ninu ara. 4 Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ. 5 Ki ọkàn nyin ki o máṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ. 6 Nitorina ni awa ṣe nfi igboiya wipe, Oluwa li oluranlọwọ mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? 7 Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn. 8 Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai. 9 Ẹ máṣe jẹ ki a fi onirũru ati ẹkọ́ àjeji gbá nyin kiri. Nitori o dara ki a mu nyin li ọkàn le nipa ore-ọfẹ, kì iṣe nipa onjẹ, ninu eyiti awọn ti o ti nrìn ninu wọn kò li ère. 10 Awa ni pẹpẹ kan, ninu eyi ti awọn ti nsìn agọ́ kò li agbara lati mã jẹ. 11 Nitoripe ara awọn ẹran wọnni, ẹ̀jẹ eyiti olori alufa mu wá si ibi mimọ́ nitori ẹ̀ṣẹ, a sun wọn lẹhin ibudo. 12 Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ sọ awọn enia di mimọ́, o jìya lẹhin bode. 13 Nitorina ẹ jẹ ki a jade tọ̀ ọ lọ lẹhin ibudo, ki a mã rù ẹ̀gan rẹ̀. 14 Nitoripe awa kò ni ilu ti o wà titi nihin, ṣugbọn awa nwá eyiti mbọ̀. 15 Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀. 16 Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ. 17 Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin. 18 Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo. 19 Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.

Ìdágbére

20 Njẹ Ọlọrun alafia, ẹniti o tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan, ti inu okú wá, nipa ẹ̀jẹ majẹmu aiyeraiye, ani Oluwa wa Jesu, 21 Ki o mu nyin pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀, ki o mã ṣiṣẹ ohun ti iṣe itẹwọgba niwaju rẹ̀ ninu wa nipasẹ Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin. 22 Emi si mbẹ nyin, ará, ẹ gbà ọ̀rọ iyanju mi; nitori iwe kukuru ni mo kọ si nyin. 23 Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin. 24 Ẹ kí gbogbo awọn ti nṣe olori nyin, ati gbogbo awọn enia mimọ́. Awọn ti o ti Itali wá kí nyin. 25 Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Jakọbu 1

Ìkíni

1 JAKỌBU, iranṣẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi Oluwa, si awọn ẹ̀ya mejila ti o túka kiri, alafia.

Igbagbọ ati Ọgbọ́n

2 Ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba bọ́ sinu onirũru idanwò, ẹ kà gbogbo rẹ̀ si ayọ; 3 Ki ẹ si mọ̀ pe, idanwò igbagbọ́ nyin nṣiṣẹ sũru. 4 Ṣugbọn ẹ jẹ ki sũru ki o ṣe iṣẹ aṣepé, ki ẹnyin ki o le jẹ pipe ati ailabuku, ki o má kù ohun kan fun ẹnikẹni. 5 Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bère lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia ni ọ̀pọlọpọ, ti kì isi ibaniwi; a o si fifun u. 6 Ṣugbọn ki o bère ni igbagbọ́, li aiṣiyemeji rara. Nitori ẹniti o nṣiyemeji dabi ìgbi omi okun, ti nti ọwọ́ afẹfẹ bì siwa bì sẹhin ti a si nrú soke. 7 Nitori ki iru enia bẹ̃ máṣe rò pe, on yio ri ohunkohun gbà lọwọ Oluwa;

Mẹ̀kúnnù ati Ọlọ́rọ̀

8 Enia oniyemeji jẹ alaiduro ni ọ̀na rẹ̀ gbogbo. 9 Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀. 10 Ati ọlọrọ̀, ni irẹ̀silẹ rẹ̀, nitori bi itanná koriko ni yio kọja lọ. 11 Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀.

Ìlò Ìdánwò

12 Ibukún ni fun ọkunrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yege, yio gbà ade ìye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ. 13 Ki ẹnikẹni ti a danwò máṣe wipe, Lati ọwọ́ Ọlọrun li a ti dán mi wò: nitori a kò le fi buburu dán Ọlọrun wò, on na kì isi idán ẹnikẹni wò: 14 Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ. 15 Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba lóyun, a bí ẹ̀ṣẹ: ati ẹ̀ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bí ikú. 16 Ki a má ṣe tan nyin jẹ, ẹnyin ará mi olufẹ. 17 Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida. 18 Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀.

Gbígbọ́ ati Ṣíṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọrun

19 Ẹnyin mọ eyi, ẹnyin ará mi olufẹ; ṣugbọn jẹ ki olukuluku enia ki o mã yara lati gbọ́, ki o lọra lati fọhùn, ki o lọra lati binu: 20 Nitori ibinu enia kì iṣiṣẹ ododo Ọlọrun. 21 Nitorina ẹ fi gbogbo ẽri ati buburu aṣeleke lelẹ li apakan, ki ẹ si fi ọkàn tutù gbà ọ̀rọ na ti a gbin, ti o le gbà ọkàn nyin là. 22 Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ. 23 Nitori bi ẹnikan ba jẹ olugbọ́ ọ̀rọ na, ti kò si jẹ oluṣe, on dabi ọkunrin ti o nṣakiyesi oju ara rẹ̀ ninu awojiji: 24 Nitori o ṣakiyesi ara rẹ̀, o si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna o si gbagbé bi on ti ri. 25 Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin omnira nì, ti o si duro ninu rẹ̀, ti on kò jẹ olugbọ́ ti ngbagbé, bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ̀ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ̀. 26 Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni. 27 Ìsin mimọ́ ati ailẽri niwaju Ọlọrun ati Baba li eyi, lati mã bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati lati pa ara rẹ̀ mọ́ lailabawọn kuro li aiyé.

Jakọbu 2

Ẹ Má Ṣe Ojuṣaaju

1 ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe fi iṣãju enia dì igbagbọ́ Oluwa wa Jesu Kristi Oluwa ogo mu. 2 Nitori bi ọkunrin kan ba wá si ajọ nyin, pẹlu oruka wura, ati aṣọ daradara, ti talakà kan si wá pẹlu li aṣọ ẽri; 3 Ti ẹnyin si bu iyìn fun ẹniti o wọ̀ aṣọ daradara, ti ẹ si wipe, Iwọ joko nihinyi ni ibi daradara; ti ẹ si wi fun talakà na pe, Iwọ duro nibẹ̀, tabi joko nihin labẹ apoti itisẹ mi: 4 Ẹnyin kò ha nda ara nyin si meji ninu ara nyin, ẹ kò ha si di onidajọ ti o ni ero buburu? 5 Ẹ fi etí silẹ, ẹnyin ará mi olufẹ, Ọlọrun kò ha ti yàn awọn talakà aiye yi ṣe ọlọrọ̀ ni igbagbọ́, ati ajogun ijọba na, ti o ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ? 6 Ṣugbọn ẹnyin ti bù talakà kù. Awọn ọlọrọ̀ kò ha npọ́n nyin loju, nwọn kò ha si nwọ́ nyin lọ si ile ẹjọ? 7 Nwọn kò ha nsọ ọrọ-odi si orukọ rere nì ti a fi npè nyin? 8 Ṣugbọn bi ẹnyin ba nmu olú ofin nì ṣẹ gẹgẹ bi iwe-mimọ́, eyini ni, Iwọ fẹ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ, ẹnyin nṣe daradara. 9 Ṣugbọn bi ẹnyin ba nṣe ojuṣãju enia, ẹnyin ndẹ̀ṣẹ, a si nda nyin lẹbi nipa ofin bi arufin. 10 Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ́, ti o si rú ọ̀kan, o jẹbi gbogbo rẹ̀. 11 Nitori ẹniti o wipe, Máṣe ṣe panṣaga, on li o si wipe, Máṣe pania. Njẹ bi iwọ kò ṣe panṣaga, ṣugbọn ti iwọ pania, iwọ di arufin. 12 Ẹ mã sọrọ bẹ̃, ẹ si mã huwa bẹ̃, bi awọn ti a o fi ofin omnira dá li ẹjọ. 13 Nitori ẹniti kò ṣãnu, li a o ṣe idajọ fun laisi ãnu; ãnu nṣogo lori idajọ.

Igbagbọ ati Iṣẹ́

14 Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi? 15 Bi arakunrin tabi arabinrin kan ba wà ni ìhoho, ti o si ṣe aili onjẹ õjọ, 16 Ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ? 17 Bẹ̃ si ni igbagbọ́, bi kò ba ni iṣẹ, o kú ninu ara. 18 Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi. 19 Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri. 20 Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni? 21 Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ? 22 Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé. 23 Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun. 24 Njẹ ẹnyin ri pe nipa iṣẹ li a ndá enia lare, kì iṣe nipa igbagbọ́ nikan. 25 Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran? 26 Nitori bi ara li aisi ẹmí ti jẹ́ okú, bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni igbagbọ́ li aisi iṣẹ jẹ́ okú.

Jakọbu 3

Ahọ́n

1 ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe jẹ olukọni pipọ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awa ni yio jẹbi ju. 2 Nitori ninu ohun pipọ ni gbogbo wa nṣì i ṣe. Bi ẹnikan kò ba ṣì i ṣe ninu ọ̀rọ, on na li ẹni pipé, on li o si le kó gbogbo ara ni ijanu. 3 Bi a bá si fi ijanu bọ̀ ẹṣin li ẹnu, ki nwọn ki o le gbọ́ ti wa, gbogbo ara wọn li awa si nyi kiri pẹlu. 4 Kiyesi awọn ọkọ̀ pẹlu, bi nwọn ti tobi to nì, ti a si nti ọwọ ẹfũfu lile gbá kiri, itọkọ̀ kekere li a fi ndari wọn kiri, sibikibi ti o bá wù ẹniti ntọ́ ọkọ̀. 5 Bẹ̃ pẹlu li ahọn jẹ ẹ̀ya kekere, o si nfọnnu ohun nla. Wo igi nla ti iná kekere nsun jóna! 6 Iná si ni ahọ́n, aiye ẹ̀ṣẹ si ni: li arin awọn ẹ̀ya ara wa, li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ́ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apãdi si ntinabọ on na. 7 Nitori olukuluku ẹda ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ejò, ati ti ohun ti mbẹ li okun, li a ntù loju, ti a si ti tù loju lati ọwọ ẹda enia wá. 8 Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni. 9 On li awa fi nyìn Oluwa ati Baba, on li a si fi mbú enia, ti a dá li aworan Ọlọrun. 10 Lati ẹnu kanna ni iyìn ati ẽbú ti njade. Ẹnyin ará mi, nkan wọnyi kò yẹ ki o ri bẹ̃. 11 Orisun a ha mã sun omi tutù ati omiró jade lati ojusun kanna wá bi? 12 Ẹnyin ará mi, igi ọpọtọ ha le so eso olifi bi? tabi ajara le so eso ọpọtọ? bẹ̃li orisun kan kò le sun omiró ati omi tutù.

Ọgbọ́n láti Òkè Wá

13 Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn. 14 Ṣugbọn bi ẹnyin ba ni owú kikorò ati ìja li ọkàn nyin, ẹ máṣe ṣeféfe, ẹ má si ṣeke si otitọ. 15 Ọgbọ́n yi ki iṣe eyiti o ti oke sọkalẹ wá, ṣugbọn ti aiye ni, ti ara ni, ti ẹmí èṣu ni. 16 Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà. 17 Ṣugbọn ọgbọ́n ti o ti oke wá, a kọ́ mọ́, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì isí iṣoro lati bẹ̀, a kún fun ãnu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe. 18 Eso ododo li a ngbìn li alafia fun awọn ti nṣiṣẹ alafia.

Jakọbu 4

Bíbá Ayé Rẹ́

1 NIBO ni ogun ti wá, nibo ni ija si ti wá larin nyin? lati inu eyi ha kọ? lati inu ifẹkufẹ ara nyin, ti njagun ninu awọn ẹ̀ya-ara nyin? 2 Ẹnyin nfẹ, ẹ kò si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ kò si le ni: ẹnyin njà, ẹnyin si njagun; ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère. 3 Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin. 4 Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun. 5 Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa? 6 Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn. 7 Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin. 8 Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji. 9 Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu. 10 Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga.

Dídá Arakunrin Wa Lẹ́jọ́

11 Ará, ẹ máṣe sọ̀rọ ibi si ara nyin. Ẹniti o ba nsọ̀rọ ibi si arakunrin rẹ̀, ti o si ndá arakunrin rẹ̀ lẹjọ, o nsọ̀rọ ibi si ofin, o si ndá ofin lẹjọ; ṣugbọn bi iwọ ba ndá ofin lẹjọ, iwọ kì iṣe oluṣe ofin, bikoṣe onidajọ. 12 Olofin ati onidajọ kanṣoṣo ni mbẹ, ani ẹniti ó le gbala ti o si le parun; ṣugbọn tani iwọ ti ndá ẹnikeji rẹ lẹjọ?

Ìkìlọ̀ nípa Fífọ́nnu

13 Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin tí nwipe, Loni tabi lọla awa ó lọ si ilu bayi, a o si ṣe ọdún kan nibẹ, a o si ṣòwo, a o si jère: 14 Nigbati ẹnyin kò mọ̀ ohun ti yio hù lọla. Kili ẹmí nyin? Ikũku sá ni nyin, ti o hàn nigba diẹ, lẹhinna a si túka lọ. 15 Eyi ti ẹ bá fi wipe, bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lãye, a o si ṣe eyi tabi eyini. 16 Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nṣeféfe ninu ifọnnu nyin: gbogbo irú iṣeféfe bẹ̃, ibi ni. 17 Nitorina ẹniti o ba mọ̀ rere iṣe ti kò si ṣe, ẹ̀ṣẹ ni fun u.

Jakọbu 5

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọlọ́rọ̀

1 Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin. 2 Ọrọ̀ nyin dibajẹ, kòkoro si ti jẹ̀ aṣọ nyin. 3 Wura on fadaka nyin diparà; iparà wọn ni yio si ṣe ẹlẹri si nyin, ti yio si jẹ ẹran ara nyin bi iná. Ẹnyin ti kó iṣura jọ dè ọjọ ikẹhin. 4 Kiyesi i, ọ̀ya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko nyin, eyiti ẹ kò san, nke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun. 5 Ẹnyin ti jẹ adùn li aiye, ẹnyin si ti fi ara nyin fun aiye jijẹ; ẹnyin ti bọ́ li ọjọ pipa. 6 Ẹnyin ti da ẹbi fun olododo, ẹ si ti pa a; on kò kọ oju ija si nyin.

Sùúrù ati Adura

7 Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo. 8 Ẹnyin pẹlu ẹ mu sũru; ẹ fi ọkàn nyin balẹ̀: nitori ipadawa Oluwa kù si dẹdẹ. 9 Ẹ máṣe kùn si ọmọnikeji nyin, ará, ki a má bã dá nyin lẹbi: kiyesi i, onidajọ duro li ẹnu ilẹkun. 10 Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru. 11 Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu. 12 Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi. 13 Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́. 14 Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: 15 Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i. 16 Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ. 17 Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa. 18 O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade. 19 Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada; 20 Jẹ ki o mọ̀ pe, ẹniti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣina rẹ̀, yio gbà ọkàn kan là kuro lọwọ ikú, yio si bò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.

1 Peteru 1

1 PETERU, Aposteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti nṣe atipo ti nwọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia, Asia, ati Bitinia, 2 Gẹgẹ bi ìmọtẹlẹ Ọlọrun Baba, nipa isọdimimọ́ Ẹmí, si igbọran ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ Jesu Kristi: Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bi si i fun nyin.

Ìrètí tí Ó Wà Láàyè

3 Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú, 4 Sinu ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kì iṣá, ti a ti fi pamọ́ li ọrun dè nyin, 5 Ẹnyin ti a npamọ́ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ́ si igbala, ti a mura lati fihàn ni igba ikẹhin. 6 Ninu eyiti ẹnyin nyọ̀ pipọ, bi o tilẹ ṣe pe nisisiyi fun igba diẹ, niwọnbi o ti yẹ, a ti fi ọ̀pọlọpọ idanwo bà nyin ninu jẹ: 7 Ki idanwò igbagbọ́ nyin, ti o ni iye lori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe iná li a fi ndán a wò, ki a le ri i fun iyìn, ati ọlá, ati ninu ogo ni igba ifarahàn Jesu Kristi: 8 Ẹniti ẹnyin fẹ lairi, ẹniti ẹnyin gbagbọ, bi o tilẹ ṣepe ẹ kò ri i nisisiyi, ẹnyin si nyọ ayọ̀ ti a kò le fi ẹnu ṣo, ti o si kun fun ogo: 9 Ẹnyin si ngbà opin igbagbọ́ nyin, ani igbala ọkàn nyin; 10 Igbala ti awọn woli wadi, ti nwọn si wá jinlẹ, awọn ti nwọn sọ asọtẹlẹ ti ore-ọfẹ ti mbọ̀ fun nyin: 11 Nwọn nwadi igba wo tabi irú sã wo ni Ẹmi Kristi ti o wà ninu wọn ntọ́ka si, nigbati o jẹri ìya Kristi tẹlẹ ati ogo ti yio tẹlé e. 12 Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò.

Ìpè sí Ìgbé-Ayé Mímọ́

13 Nitorina ẹ di ọkàn nyin li amure, ẹ mã wa li airekọja, ki ẹ si mã reti ore-ọfẹ nì titi de opin, eyiti a nmu bọ̀ fun nyin wá ni igba ifarahàn Jesu Kristi: 14 Bi awọn eleti ọmọ, li aifi ara nyin dáṣà bi ifẹkufẹ atijọ ninu aimọ̀ nyin: 15 Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo: 16 Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹ jẹ mimọ́; nitoriti mo jẹ mimọ́. 17 Bi ẹnyin ba si nkepè Baba, ẹniti nṣe idajọ gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku, li aiṣe ojuṣaju enia, ẹ mã lo igba atipo nyin ni ìbẹru: 18 Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin, 19 Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi; 20 Ẹniti a ti mọ̀ tẹlẹ nitõtọ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ṣugbọn ti a fihan ni igba ikẹhin wọnyi nitori nyin, 21 Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun. 22 Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá. 23 Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro. 24 Nitoripe gbogbo ẹran ara dabi koriko, ati gbogbo ogo rẹ̀ bi itanná koriko. Koriko a mã gbẹ, itanná rẹ̀ a si rẹ̀ silẹ: 25 Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa duro titi lai. Ọ̀rọ yi na si ni ihinrere ti a wãsu fun nyin.

1 Peteru 2

Òkúta Ààyè ati Orílẹ̀-Èdè Mímọ́

1 NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo. 2 Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala, 3 Bi ẹnyin ba ti tọ́ ọ wò pe, olõre li Oluwa: 4 Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye, 5 Ẹnyin pẹlu, bi okuta ãye, li a kọ ni ile ẹmí, alufa mimọ́, lati mã ru ẹbọ ẹmí, ti iṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun nipa Jesu Kristi. 6 Nitori o mbẹ ninu iwe-mimọ́ pe, Kiyesi i, Mo fi pàtaki okuta igunle, àṣayan, iyebiye, lelẹ ni Sioni: ẹniti o ba si gbà a gbọ́ oju kì yio ti i. 7 Nitorina fun ẹnyin ti o gbagbọ́, ọla ni: ṣugbọn fun awọn ti kò gbagbọ́, okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o di pàtaki igunle, 8 Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu. 9 Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn: 10 Ẹnyin ti kì iṣe enia nigbakan rí, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin di enia Ọlọrun, ẹnyin ti kò ti ri ãnu gbà ri, ṣugbọn nisisiyi ẹ ti ri ãnu gbà.

Ẹ Jẹ́ Iranṣẹ Ọlọrun

11 Olufẹ, mo bẹ̀ nyin, bi alejò ati bi èro, lati fà sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ti mba ọkàn jagun; 12 Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo. 13 Ẹ mã tẹriba fun gbogbo ìlana enia nitori ti Oluwa: ibãṣe fun ọba, bi fun olori; 14 Tabi fun awọn bãlẹ, bi fun awọn ti a rán lati ọdọ rẹ̀ fun igbẹsan lara awọn ti nṣe buburu, ati fun iyìn awọn ti nṣe rere. 15 Bẹ̃ sá ni ifẹ Ọlọrun, pe ni rere iṣe, ki ẹ le dá òpe awọn wère enia lẹkun: 16 Bi omnira, laisi lo omnira nyin fun ohun bibo arakàn nyin mọlẹ, ṣugbọn bi ẹrú Ọlọrun. 17 Ẹ bọ̀wọ fun gbogbo enia. Ẹ fẹ awọn ará. Ẹ bẹru Ọlọrun. Ẹ bọ̀wọ fun ọba.

Àpẹẹrẹ Ìjìyà Jesu

18 Ẹnyin ọmọ-ọ̀dọ, ẹ mã tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ìbẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu. 19 Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun. 20 Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun. 21 Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀: 22 Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀: 23 Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ: 24 Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada. 25 Nitori ẹnyin ti nṣako lọ bi agutan, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin pada si ọdọ Oluṣọ-agutan ati Biṣopu ọkàn nyin.

1 Peteru 3

Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Ọkọ ati Aya

1 BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn, 2 Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin: 3 Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀; 4 Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun. 5 Nitori bayi li awọn obinrin mimọ́ igbãni pẹlu, ti nwọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn li ọ̀ṣọ́, nwọn a mã tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn. 6 Gẹgẹ bi Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, ti o npè e li oluwa: ọmọbinrin ẹniti ẹnyin iṣe, bi ẹnyin ba nṣe rere, ti ohunkohun kò si dẹruba nyìn. 7 Bẹ̃ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ mã fi oye bá awọn aya nyin gbé, ẹ mã fi ọla fun aya, bi ohun èlo ti kò lagbara, ati pẹlu bi ajumọ-jogun ore-ọfẹ ìye; ki adura nyin ki o má bã ni ìdena.

Ìjìyà Nítorí Òdodo

8 Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ. 9 Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún. 10 Nitori, Ẹniti yio ba fẹ ìye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rẹ̀ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ̀ kuro ni sisọ ọrọ ẹ̀tan: 11 Ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mã ṣe rere; ki o mã wá alafia, ki o si mã lepa rẹ̀. 12 Nitori oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, etí rẹ̀ si ṣí si ẹbẹ wọn: ṣugbọn oju Oluwa nwo awọn ti nṣe buburu. 13 Tani yio si ṣe nyin ni ibi, bi ẹnyin ba jẹ onítara si ohun rere? 14 Ṣugbọn bi ẹnyin ba jìya nitori ododo, alafia ni: ẹ máṣe bẹru wọn, ki ẹ má si ṣe kọminu; 15 Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru. 16 Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi. 17 Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ. 18 Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí: 19 Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu: 20 Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ; 21 Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi: 22 Ẹniti o ti lọ si ọrun, ti o si mbẹ li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; awọn angẹli, ati awọn ọlọlá, ati awọn alagbara si ntẹriba fun.

1 Peteru 4

Ìríjú Rere

1 NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ; 2 Ki ẹnyin ki o máṣe fi ìgba aiye nyin iyokù wà ninu ara mọ́ si ifẹkufẹ enia, bikoṣe si ifẹ Ọlọrun. 3 Nitori igba ti o ti kọja ti to fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrìn ninu iwa wọ̀bia, ifẹkufẹ, ọti amupara, ìrède oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ìbọriṣa ti iṣe ohun irira. 4 Eyi ti o yà wọn lẹnu pe ẹnyin kò ba wọn súré sinu iru aṣejù iwa wọbia wọn, ti nwọn sì nsọrọ nyin ni buburu, 5 Awọn ẹniti yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú. 6 Nitori eyi li a sá ṣe wasu ihinrere fun awọn okú, ki a le ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi enia nipa ti ara, ṣugbọn ki nwọn ki o le wà lãye si Ọlọrun nipa ti ẹmí. 7 Ṣugbọn opin ohun gbogbo kù si dẹ̀dẹ: nitorina ki ẹnyin ki o wà li airekọja, ki ẹ si mã ṣọra ninu adura. 8 Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ. 9 Ẹ mã ṣe ara nyin li alejò laisi ikùn sinu. 10 Bi olukuluku ti ri ẹ̀bun gbà, bẹ̃ni ki ẹ mã ṣe ipinfunni rẹ̀ larin ara nyin, bi iriju rere ti onirũru ore-ọfẹ Ọlọrun. 11 Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin.

Ìjìyà Gẹ́gẹ́ Bí Onigbagbọ

12 Olufẹ, ẹ máṣe ka idanwò iná ti mbẹ larin nyin eyiti o de si nyin lati dan nyin wò bi ẹnipe ohun àjeji li o de bá nyin: 13 Ṣugbọn niwọnbi ẹnyin ti jẹ alabapin ìya Kristi, ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o le yọ̀ ayọ̀ pipọ nigbati a ba fi ogo rẹ̀ hàn. 14 Bi a ba ngàn nyin nitori orukọ Kristi, ẹni ibukun ni nyin; nitori Ẹmí ogo ati ti Ọlọrun bà le nyin: nipa tiwọn nwọn nsọ̀rọ rẹ̀ ni ibi, ṣugbọn nipa tinyin a nyìn i logo. 15 Ṣugbọn ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ninu nyin ki o jìya bi apania, tabi bi olè, tabi bi oluṣe-buburu, tabi bi ẹniti ntojubọ ọ̀ran ẹlomiran. 16 Ṣugbọn bi o ba jìya bi Kristiani, ki oju ki o máṣe tì i; ṣugbọn ki o kuku yìn Ọlọrun logo ni orukọ yi. 17 Nitoriti ìgba na de, ti idajọ yio bẹ̀rẹ lati ile Ọlọrun wá: bi o ba si tète ti ọdọ wa bẹ̀rẹ, opin awọn ti kò gbà ihinrere Ọlọrun gbọ́ yio ha ti ri? 18 Biobaṣepe agbara káka li a fi gba olododo là, nibo ni alaiwà-bi-Ọlọrun on ẹlẹṣẹ yio gbé yọju si? 19 Nitorina ẹ jẹ ki awọn ti njìya gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun, fi ọkàn wọn le e lọwọ pẹlu ni rere iṣe, bi ẹnipe fun Ẹlẹda olõtọ.

1 Peteru 5

Bíbọ́ Agbo Aguntan Ọlọrun

1 AWỌN alàgba ti mbẹ lãrin nyin ni mo bẹ̀, emi ẹniti iṣe alàgba bi ẹnyin, ati ẹlẹri ìya Kristi, ati alabapin ninu ogo ti a o fihàn: 2 Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan. 3 Bẹ̃ni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo. 4 Nigbati olori Oluṣọ-agutan ba si fi ara hàn, ẹnyin ó gbà ade ogo ti kì iṣá. 5 Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ. 6 Nitorina ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki on ki o le gbé nyin ga li akokò. 7 Ẹ mã kó gbogbo aniyan nyin le e; nitoriti on nṣe itọju nyin. 8 Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri: 9 Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ. 10 Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ. 11 Tirẹ̀ li ogo ati agbara titi lailai. Amin.

Ìdágbére

12 Nipa Silfanu, arakunrin wa olõtọ gẹgẹbi mo ti ka a si, ni mo kọwe kukuru si nyin, ti mo ngbà nyin niyanju, ti mo si njẹri pe, eyi ni otitọ ore-ọfẹ Ọlọrun: ẹ duro ṣinṣin ninu rẹ̀. 13 Ijọ ti mbẹ ni Babiloni, ti a yàn pẹlu nyin, kí nyin; bẹ̃ si ni Marku ọmọ mi pẹlu. 14 Ẹ fi ifẹnukonu ifẹ kí ara nyin. Amin.

2 Peteru 1

Ìkíni

1 SIMONI Peteru, iranṣẹ ati Aposteli Jesu Kristi, si awọn ti o ti gbà irú iyebiye igbagbọ́ kanna pẹlu wa, ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Olugbala: 2 Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bisi i fun nyin ninu ìmọ Ọlọrun, ati ti Jesu Oluwa wa,

Ìpè ati Yíyàn Onigbagbọ

3 Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀: 4 Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ. 5 Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere; 6 Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru; 7 Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji. 8 Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi. 9 Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkẽre, o si ti gbagbé pe a ti wẹ̀ on nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ atijọ. 10 Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai. 11 Nitori bayi li a ó pese fun nyin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi. 12 Nitorina emi ó mã mura lati mã mu nkan wọnyi wá si iranti nyin nigbagbogbo bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ wọn, ti ẹsẹ nyin si mulẹ ninu otitọ ti ẹnyin ni. 13 Emi si rò pe o yẹ, niwọn igbati emi ba mbẹ ninu agọ́ yi, lati mã fi iranti rú nyin soke; 14 Bi emi ti mọ̀ pe, bibọ́ agọ́ mi yi silẹ kù si dẹdẹ, ani bi Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mi. 15 Emi o si mã ṣãpọn pẹlu, ki ẹnyin ki o le mã ranti nkan wọnyi nigbagbogbo lẹhin ikú mi.

Ògo Kristi ati Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀

16 Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe. 17 Nitoriti o gbà ọlá on ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigbati irú ohùn nì fọ̀ si i lati inu ogo nla na wá pe, Eyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si jọjọ. 18 Ohùn yi ti o ti ọrun wá li awa si gbọ́, nigbati awa mbẹ pẹlu rẹ̀ lori òke mimọ́ na. 19 Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin. 20 Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi, pe kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ́ ti o ni itumọ̀ ikọkọ. 21 Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.

2 Peteru 2

Àwọn Wolii Èké ati Olùkọ́ni Èké

1 ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn. 2 Ọpọlọpọ ni yio si mã tẹle ìwa wọbia wọn; nipa awọn ẹniti a o fi mã sọ ọrọ-odi si ọ̀na otitọ. 3 Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé. 4 Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ; 5 Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; 6 Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; 7 O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ: 8 (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́): 9 Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ: 10 Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye. 11 Bẹni awọn angẹli bi nwọn ti pọ̀ ni agbara ati ipá tõ nì, nwọn kò dá wọn lẹjọ ẹ̀gan niwaju Oluwa. 12 Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn. 13 Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin; 14 Awọn oloju ti o kún fun panṣaga, ti kò si le dẹkun ẹ̀ṣẹ idá; ti ntàn awọn ọkàn ti kò fi ẹsẹ mulẹ jẹ: awọn ti nwọn ni ọkàn ti o ti fi ojukòkoro kọ́ra; awọn ọmọ ègún: 15 Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo; 16 Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ̀: odi kẹtẹkẹtẹ fi ohùn enia sọ̀rọ, o si fi opin si were wolĩ na. 17 Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai. 18 Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina. 19 Nwọn a mã ṣe ileri omnira fun wọn, nigbati awọn pãpã jẹ ẹrú idibajẹ́: nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú. 20 Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ. 21 Nitori ìba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ̀ ọ̀na ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ̀ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ́ ti a fifun wọn. 22 Owe otitọ nì ṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbì ara rẹ̀; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹ̀ mọ́ sinu àfọ ninu ẹrẹ̀.

2 Peteru 3

Ìlérí Pé Oluwa Yóo tún Pada Wá

1 OLUFẸ, eyi ni iwe keji ti mo nkọ si nyin; ninu mejeji na li emi nrú inu funfun nyin soke nipa riran nyin leti: 2 Ki ẹnyin ki o le mã ranti ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn woli mimọ́ sọ ṣaju, ati ofin Oluwa ati Olugbala wa lati ọdọ awọn aposteli nyin: 3 Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn, 4 Nwọn o si mã wipe, Nibo ni ileri wíwa rẹ̀ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà rí lati ìgba ọjọ ìwa. 5 Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi: 6 Nipa eyi ti omi bo aiye ti o wà nigbana, ti o si ṣegbe: 7 Ṣugbọn awọn ọrun ati aiye, ti mbẹ nisisiyi, nipa ọ̀rọ kanna li a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ́ dè ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. 8 Ṣugbọn, olufẹ, ẹ máṣe gbagbe ohun kan yi, pe ọjọ kan lọdọ Oluwa bi ẹgbẹ̀run ọdún li o ri, ati ẹgbẹ̀run ọdún bi ọjọ kan. 9 Oluwa kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti ikà a si ijafara; ṣugbọn o nmu sũru fun nyin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada. 10 Ṣugbọn ọjọ Oluwa mbọ̀wá bi olè li oru; ninu eyi ti awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yíyọ, aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rẹ̀ yio si jóna lulu. 11 Njẹ bi gbogbo nkan wọnyi yio ti yọ́ nì, irú enia wo li ẹnyin iba jẹ ninu ìwa mimọ́ gbogbo ati ìwa-bi-Ọlọrun, 12 Ki ẹ mã reti, ki ẹ si mã mura giri de díde ọjọ Ọlọrun, nitori eyiti awọn ọ̀run yio gbiná, ti nwọn yio di yíyọ́, ti awọn imọlẹ rẹ̀ yio si ti inu õru gbigbona gidigidi di yíyọ? 13 Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa nreti awọn ọrun titun ati aiye titun, ninu eyiti ododo ngbé. 14 Nitorina, olufẹ, bi ẹnyin ti nreti irú nkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le bá nyin li alafia, li ailabawọn, ati li ailàbuku li oju rẹ̀. 15 Ki ẹ si mã kà a si pe, sũru Oluwa wa igbala ni; bi Paulu pẹlu, arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si nyin, gẹgẹ bi ọgbọ́n ti a fifun u; 16 Bi o ti nsọ̀rọ nkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ̀ gbogbo; ninu eyi ti ohun miran ti o ṣòro lati yéni gbé wà, eyiti awọn òpè ati awọn alaiduro nibikan nlọ́, bi nwọn ti nlọ́ iwe mimọ́ iyoku, si iparun ara wọn. 17 Nitorina ẹnyin olufẹ, bi ẹnyin ti mọ̀ nkan wọnyi tẹlẹ ẹ mã kiyesara, ki a má ba fi ìṣina awọn enia buburu fà nyin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ni iduro ṣinṣin nyin. 18 Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.

1 Johanu 1

Ọ̀rọ̀ Ìyè

1 EYITI o ti wà li àtetekọṣe, ti awa ti gbọ́, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ́ wa si ti dìmu, niti Ọrọ ìye; 2 (Ìye na si ti farahàn, awa si ti ri i, awa si njẹri, awa si nsọ ti ìye ainipẹkun na fun nyin, ti o ti mbẹ lọdọ Baba, ti o si farahàn fun wa;) 3 Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. 4 Awa si kọwe nkan wọnyi si nyin, ki ayọ̀ nyin ki o le di kikún.

Ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun

5 Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si njẹ́ fun nyin, pe imọlẹ li Ọlọrun, òkunkun kò si sí lọdọ rẹ̀ rara. 6 Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ: 7 Ṣugbọn bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo. 8 Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa. 9 Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo. 10 Bi awa ba wipe awa kò dẹṣẹ̀, awa mu u li eke, ọ̀rọ rẹ̀ kò si si ninu wa.

1 Johanu 2

Jesu Alágbàwí Wa

1 ẸNYIN ọmọ mi, iwe nkan wọnyi ni mo kọ si nyin, ki ẹ má bã dẹṣẹ̀. Bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ̀, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo: 2 On si ni ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa: kì si iṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araiye pẹlu. 3 Nipa eyi li a si mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba npa ofin rẹ̀ mọ́. 4 Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀. 5 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba npa ofin rẹ̀ mọ́, lara rẹ̀ li a gbé mu ifẹ Ọlọrun pé nitõtọ. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa mbẹ ninu rẹ̀, 6 Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rẹ̀, on na pẹlu si yẹ lati mã rìn gẹgẹ bi on ti rìn.

Òfin Tuntun

7 Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́. 8 Ẹ̀wẹ, ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, eyiti iṣe otitọ ninu rẹ̀ ati ninu nyin, nitori òkunkun nkọja lọ, imọlẹ otitọ si ti ntàn. 9 Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o mbẹ ninu òkunkun titi fi di isisiyi. 10 Ẹniti o ba fẹran arakunrin rẹ̀, o ngbe inu imọlẹ, kò si si ohun ikọsẹ̀ ninu rẹ̀. 11 Ṣugbọn ẹniti o ba korira arakunrin rẹ̀ o ngbe inu òkunkun, o si nrìn ninu òkunkun, kò si mọ̀ ibiti on nrè, nitoriti òkunkun ti fọ ọ li oju.

Àwọn Tí A Kọ Ìwé Yìí sí

12 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitoriti a dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin nitori orukọ rẹ̀. 13 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin ti ṣẹgun ẹni buburu nì. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitori ẹnyin ti mọ̀ Baba. 14 Emi kọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi ti kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li agbara, ti ọ̀rọ Ọlọrun si duro ninu nyin, ti ẹ si ṣẹgun ẹni buburu nì.

Afẹ́ Ayé

15 Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ̀. 16 Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye. 17 Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai.

Alátakò Kristi

18 Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi. 19 Nwọn ti ọdọ wa jade, ṣugbọn nwọn ki iṣe ará wa; nitori nwọn iba ṣe ará wa, nwọn iba bá wa duro: ṣugbọn nwọn jade ki a le fi wọn hàn pe gbogbo nwọn ki iṣe ará wa. 20 Ṣugbọn ẹnyin ni ifororo-yan lati ọdọ Ẹni Mimọ́ nì wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo. 21 Emi kò kọwe si nyin nitoripe ẹnyin kò mọ̀ otitọ, ṣugbọn nitoriti ẹnyin mọ̀ ọ, ati pe kò si eke ninu otitọ. 22 Tani eke, bikoṣe ẹniti o ba sẹ́ pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Aṣodisi-Kristi, ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ. 23 Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu. 24 Ṣugbọn ẹnyin, ki eyini ki o mã gbe inu nyin, ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba ngbe inu nyin, ẹnyin ó si duro pẹlu ninu Ọmọ ati ninu Baba. 25 Eyi si ni ileri na ti o ti ṣe fun wa, ani ìye ainipẹkun. 26 Nkan wọnyi ni mo kọwe si nyin niti awọn ti ntàn nyin jẹ. 27 Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀.

Àwọn ọmọ Ọlọrun

28 Ati nisisiyi, ẹnyin ọmọ mi, ẹ mã gbe inu rẹ̀; pe, nigbati on o ba farahàn, ki a le ni igboiya niwaju rẹ̀, ki oju má si tì wa niwaju rẹ̀ ni igba wiwá rẹ̀. 29 Bi ẹnyin ba mọ̀ pe olododo ni on, ẹ mọ̀ pe a bi olukuluku ẹniti nṣe ododo nipa rẹ̀.

1 Johanu 3

1 Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ̃ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ̀ wa, nitoriti ko mọ̀ ọ. 2 Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri. 3 Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́. 4 Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ o nrú ofin pẹlu: nitori ẹ̀ṣẹ ni riru ofin. 5 Ẹnyin si mọ̀ pe, on farahàn lati mu ẹ̀ṣẹ kuro; ẹ̀ṣẹ kò si si ninu rẹ̀. 6 Ẹnikẹni ti o ba ngbé inu rẹ̀ ki idẹṣẹ; ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ kò ri i, bẹ̃ni kò mọ̀ ọ. 7 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin: ẹniti o ba nṣe ododo, o jasi olododo, gẹgẹ bi on ti iṣe olododo. 8 Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run. 9 Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i. 10 Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.

Ẹ Fẹ́ràn Ẹnìkejì Yín

11 Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa. 12 Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo. 13 Ki ẹnu ki o máṣe yà nyin, ẹnyin ará mi, bi aiye ba korira nyin. 14 Awa mọ̀ pe awa ti rekọja lati inu ikú sinu ìye, nitoriti awa fẹràn awọn ará. Ẹniti kò ba ni ifẹ o ngbé inu ikú. 15 Ẹnikẹni ti o ba korira arakunrin rẹ̀ apania ni: ẹnyin si mọ̀ pe kò si apania ti o ni ìye ainipẹkun lati mã gbé inu rẹ̀. 16 Nipa eyi li awa mọ̀ ifẹ nitoriti o fi ẹmí rẹ̀ lelẹ fun wa: o si yẹ ki awa fi ẹmí wa lelẹ fun awọn ará. 17 Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀? 18 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ.

Ìgboyà Níwájú Ọlọrun

19 Ati nipa eyi li awa ó mọ̀ pe awa jẹ ti otitọ, ati pe awa o si dá ara wa loju niwaju rẹ̀, 20 Ninu ohunkohun ti ọkàn wa ba ndá wa lẹbi; nitoripe Ọlọrun tobi jù ọkàn wa lọ, o si mọ̀ ohun gbogbo. 21 Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun. 22 Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rẹ̀, nitoriti awa npa ofin rẹ̀ mọ́, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ̀. 23 Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa. 24 Ẹniti o ba si pa ofin rẹ̀ mọ́ ngbé inu rẹ̀, ati on ninu rẹ̀. Ati nipa eyi li awa mọ̀ pe o ngbé inu wa, nipa Ẹmí ti o fifun wa.

1 Johanu 4

Ẹ̀mí Ọlọrun ati Ẹ̀mí Alátakò Kristi

1 OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye. 2 Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni: 3 Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye. 4 Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ. 5 Ti aiye ni nwọn, nitorina ni nwọn ṣe nsọrọ bi ẹni ti aiye, aiye si ngbọ́ ti wọn. 6 Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.

Ìfẹ́ ni Ọlọrun

7 Olufẹ, ẹ jẹ ki a fẹràn ara wa: nitori ifẹ ti ọdọ Ọlọrun wá; ati gbogbo ẹniti o ba ni ifẹ, a bí i nipa ti Ọlọrun, o si mọ̀ Ọlọrun. 8 Ẹniti kò ba ni ifẹ kò mọ̀ Ọlọrun: nitoripe ifẹ ni Ọlọrun. 9 Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀. 10 Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa. 11 Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu. 12 Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa. 13 Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa. 14 Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye. 15 Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun. 16 Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀. 17 Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi. 18 Ìbẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ìbẹru ni iyà ninu. Ẹniti o bẹ̀ru kò pé ninu ifẹ. 19 Awa fẹran rẹ̀ nitori on li o kọ́ fẹran wa. 20 Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri? 21 Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.

1 Johanu 5

Igbagbọ ni Ìṣẹ́gun lórí Ayé

1 OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu. 2 Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́. 3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira. 4 Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa. 5 Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe?

Ẹ̀rí nípa Ọmọ

6 Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí. 7 Nitoripe awọn mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ̀, ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹtẹ̃ta yi si jẹ ọ̀kan 8 Nitoripe awọn mẹta li o njẹri, Ẹmí, ati omi, ati ẹ̀jẹ: awọn mẹtẹ̃ta sì fi ohun ṣọkan. 9 Bi awa ba ngbà ẹ̀rí enia, ẹ̀rí Ọlọrun tobi ju: nitọri ẹri Ọlọrun li eyi pe O ti jẹri niti Ọmọ rẹ̀. 10 Ẹniti o ba gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́, o ni ẹrí ninu ara rẹ̀: ẹniti kò ba gbà Ọlọrun gbọ́, o ti mu u li eke; nitori kò gbà ẹrí na gbọ́ ti Ọlọrun jẹ niti Ọmọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀. 12 Ẹniti o ba ni Ọmọ, o ni ìye; ẹniti kò ba si ni Ọmọ Ọlọrun, kò ni ìye.

Ìyè Ainipẹkun

13 Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́. 14 Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa: 15 Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ́ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ̀ pe awa rí ibere ti awa ti bère lọdọ rẹ̀ gbà. 16 Bi ẹnikẹni ba ri arakunrin rẹ̀ ti ndá ẹ̀ṣẹ ti kì iṣe si ikú, on o bère, On o si fun ni ìye fun awọn ti ndá ẹ̀ṣẹ ti ki iṣe si ikú. Ẹṣẹ kan mbẹ si ikú: emi kò wipe ki on ki o gbadura fun eyi. 17 Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú. 18 Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a. 19 Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì. 20 Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun. 21 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu oriṣa. Amin.

2 Johanu 1

Ìkíni

1 EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu; 2 Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi. 3 Õre-ọfẹ, ãnu, ati alafia, yio wà pẹlu wa, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati lati ọdọ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, ninu otitọ ati ninu ifẹ.

Ẹ Máa Gbé Inú Ẹ̀kọ́ Kristi

4 Mo yọ̀ gidigidi pe mo ti ri ninu awọn ọmọ rẹ ti nrin ninu otitọ, ani bi awa ti gbà ofin lati ọdọ Baba. 5 Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa. 6 Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀. 7 Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi. 8 Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà. 9 Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ. 10 Bi ẹnikẹni bá tọ̀ nyin wá, ti kò si mu ẹkọ́ yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i. 11 Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwọ́ ninu iṣẹ buburu rẹ̀.

Ìdágbére

12 Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún. 13 Awọn ọmọ arabinrin rẹ ayanfẹ ki ọ. Amin.

3 Johanu 1

Ìkíni

1 ALÀGBA si Gaiu olufẹ, ẹniti mo fẹ ninu otitọ. 2 Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ. 3 Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ. 4 Emi kò ni ayọ̀ ti o pọjù eyi lọ, ki emi ki o mã gbọ́ pe, awọn ọmọ mi nrìn ninu otitọ.

Àjọṣepọ̀

5 Olufẹ, iwọ nṣe iṣẹ igbagbọ li ohunkohun ti o bá nṣe fun awọn ti iṣe ará ati fun awọn alejò; 6 Ti nwọn jẹri ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi ìwọ bá npese fun wọn li ọna ajo wọn bi o ti yẹ nipa ti Ọlọrun, iwọ o ṣe ohun ti o dara. 7 Nitoripe nitori orukọ rẹ̀ ni nwọn ṣe jade lọ, li aigbà ohunkohun lọwọ awọn Keferi. 8 Njẹ o yẹ ki awa ki o gbà irú awọn wọnni, ki awa ki o le jẹ́ alabaṣiṣẹpọ pẹlu otitọ.

Diotirefe lòdì sí wa

9 Emi kọwe si ijọ: ṣugbọn Diotrefe, ẹniti o fẹ lati jẹ olori larin wọn, kò gbà wa. 10 Nitorina bi mo ba de, emi o mu iṣẹ rẹ̀ ti o ṣe wá si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyini kò si tẹ́ ẹ lọrùn, bẹ̃ni on tikararẹ̀ kò gbà awọn ará, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o ndá wọn lẹkun, o si nlé wọn jade kuro ninu ijọ.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú

11 Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi, bikoṣe ohun ti iṣe rere. Ẹniti o ba nṣe rere ti Ọlọrun ni: ẹniti o ba nṣe buburu kò ri Ọlọrun. 12 Demetriu li ẹri rere lọdọ gbogbo enia ati ti otitọ tikararẹ̀ pẹlu: nitõtọ, awa pẹlu si gbà ẹrí rẹ̀ jẹ; ẹnyin si mọ̀ pe otitọ ni ẹrí wa.

Ó Dìgbà Díẹ̀

13 Emi ní ohun pupọ̀ lati kọwe si ọ, ṣugbọn emi kò fẹ fi tàdãwa on kalamu kọ wọn. 14 Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju. 15 Alafia fun ọ. Awọn ọrẹ́ kí ọ. Kí awọn ọrẹ́ li ọkọ̃kan.

Juda 1

Ìkíni

1 JUDA, iranṣẹ Jesu Kristi, ati arakunrin Jakọbu, si awọn ti a pè, olufẹ ninu Ọlọrun Baba, ti a si pamọ́ fun Jesu Kristi: 2 Ki ãnu, ati alafia, ati ifẹ ki o mã bi si i fun nyin.

Ìdájọ́ fún àwọn èké olùkọ́ni

3 Olufẹ, nigbati mo fi aisimi gbogbo kọwe si nyin niti igbala ti iṣe ti gbogbo enia, nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki n si gbà nyin niyanju lati mã ja gidigidi fun igbagbọ́, ti a ti fi lé awọn enia mimọ́ lọwọ lẹ̃kanṣoṣo. 4 Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa. 5 Njẹ emi nfẹ lati rán nyin leti bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ gbogbo rẹ̀ lẹ̃kan ri, pe Oluwa, nigbati o ti gbà awọn enia kan là lati ilẹ Egipti wá, lẹhinna o run awọn ti kò gbagbọ́. 6 Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì. 7 Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun. 8 Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá. 9 Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi. 10 Ṣugbọn awọn wọnyi nsọ̀rọ-òdi si ohun gbogbo ti nwọn kò mọ̀: ṣugbọn ohun gbogbo ti nwọn mọ̀ nipa ẹda, bi ẹranko tí kò ni iyè, ninu nkan wọnyi ni nwọn di ẹni iparun. 11 Egbé ni fun wọn! nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora. 12 Awọn wọnyi li o jẹ abawọn ninu àse ifẹ nyin, nigbati nwọn mba nyin jẹ ase, awọn oluṣọ-agutan ti mbọ́ ara wọn laibẹru: ikũku laini omi, ti a nti ọwọ afẹfẹ gbá kiri: awọn igi alaileso li akoko eso, nwọn kú lẹ̃meji, a fà wọn tu ti gbongbo ti gbongbo; 13 Omi okun ti nrú, ti nhó ifõfó itiju ara wọn jade; alarinkiri irawọ, awọn ti a pa òkunkun biribiri mọ́ dè lailai. 14 Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, Oluwa mbọ̀ pẹlu ẹgbẹgbãrun awọn enia rẹ̀ mimọ́, 15 Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i. 16 Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.

Ìkìlọ̀

17 Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi; 18 Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn. 19 Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí. 20 Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́, 21 Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun. 22 Ẹ mã ṣãnu awọn ẹlomiran, ẹ mã fi ìyatọ han: 23 Ẹ mã fi ẹ̀ru gba awọn ẹlomiran là, ẹ mã fà wọn yọ kuro ninu iná; ẹ tilẹ mã korira ẹ̀wu tí ara ti sọ di ẽri.

Ibukun

24 Njẹ ti ẹniti o le pa nyin mọ́ kuro ninu ikọsẹ, ti o si le mu nyin wá siwaju ogo rẹ̀ lailabuku pẹlu ayọ nla, 25 Ti Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo, Olugbala wa, li ogo ati ọlá nla, ijọba ati agbara, nisisiyi ati titi lailai. Amin.

Ifihàn 1

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju ati Ìkíni

1 IFIHÀN ti Jesu Kristi, ti Ọlọrun fifun u, lati fihàn fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ohun ti kò le ṣaiṣẹ ni lọ̃lọ; o si ranṣẹ o si fi i hàn lati ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fun Johanu, iranṣẹ rẹ̀: 2 Ẹniti o jẹri ọ̀rọ Ọlọrun, ati ẹrí Jesu Kristi, ati ti ohun gbogbo ti o ri. 3 Olubukún li ẹniti nkà, ati awọn ti o ngbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́: nitori igba kù si dẹ̀dẹ. 4 JOHANU si ìjọ meje ti mbẹ ni Asia: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, ti o si mbọ̀wá; ati lati ọdọ awọn Ẹmí meje ti mbẹ niwaju itẹ́ rẹ̀; 5 Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, 6 Ti o si ti fi wa jẹ́ ọba ati alufa fun Ọlọrun ati Baba rẹ̀; tirẹ̀ li ogo ati ijọba lai ati lailai. Amin. 7 Kiyesi i, o mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i, ati awọn ti o gún u li ọ̀kọ pẹlu; ati gbogbo orilẹ-ede aiye ni yio si mã pohùnrere ẹkún niwaju rẹ̀. Bẹ̃na ni. Amin. 8 Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin, li Oluwa wi, ẹniti o mbẹ, ti o ti wà, ti o si mbọ̀wá, Olodumare.

Ìran Kristi

9 Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi. 10 Mo wà ninu Ẹmí li ọjọ Oluwa, mo si gbọ́ ohùn nla kan lẹhin mi, bi iró ipè, 11 O nwipe, Emi ni Alfa ati Omega, ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: ohun ti iwọ ba si ri, kọ ọ sinu iwe, ki o si rán a si awọn ijọ meje; si Efesu, ati si Smirna, ati si Pergamu, ati si Tiatira, ati si Sardi, ati si Filadelfia, ati si Laodikea. 12 Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje; 13 Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ. 14 Ori rẹ̀ ati irun rẹ̀ funfun bi ẹ̀gbọn owu, o funfun bi sno; oju rẹ̀ si dabi ọwọ́ iná; 15 Ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara, bi ẹnipe a dà a ninu ileru; ohùn rẹ̀ si dabi iró omi pupọ̀. 16 O si ni irawọ meje li ọwọ́ ọtún rẹ̀; ati lati ẹnu rẹ̀ wá ni idà oloju meji mimú ti jade: oju rẹ̀ si dabi õrùn ti o nfi agbara rẹ̀ ràn. 17 Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: 18 Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku. 19 Kọwe ohun gbogbo ti iwọ ti ri, ati ti ohun ti mbẹ, ati ti ohun ti yio hù lẹhin eyi; 20 Ohun ijinlẹ ti irawọ meje na ti iwọ ri li ọwọ́ ọtún mi, ati ọpá wura fitila meje na. Irawọ meje ni awọn angẹli ìjọ meje na: ati ọpá fitila meje na ti iwọ ri ni awọn ijọ meje.

Ifihàn 2

Iṣẹ́ sí Ìjọ Efesu

1 SI angẹli ijọ ni Efesu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o mu irawọ meje na li ọwọ́ ọtún rẹ̀, ẹniti nrìn li arin ọpá wura fitila meje na wipe, 2 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati lãlã rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rẹ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni aposteli, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn; 3 Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ. 4 Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, pe, iwọ ti fi ifẹ rẹ iṣaju silẹ. 5 Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju; bi kò si ṣe bẹ̃, emi ó si tọ̀ ọ wá, emi o si ṣí ọpá fitila rẹ kuro ni ipò rẹ̀, bikoṣe bi iwọ ba ronupiwada. 6 Ṣugbọn eyi ni iwọ ní, pe iwọ korira iṣe awọn Nikolaitani eyiti emi pẹlu si korira. 7 Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi ìye nì fun jẹ, ti mbẹ larin Paradise Ọlọrun.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Simana

8 Ati si angẹli ijọ ni Smirna kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti iṣe ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin wi, ẹniti o ti kú, ti o si tun yè: 9 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ipọnju, ati aini rẹ (ṣugbọn ọlọ́rọ̀ ni ọ) emi si mọ̀ ọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ti awọn ti nwipe Ju li awọn tikarawọn, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn jẹ́ sinagogu ti Satani. 10 Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ. 11 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun kì yio farapa ninu ikú keji.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Pẹgamu

12 Ati si angẹli ijọ ni Pergamu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni idà mimu oloju meji nì wipe, 13 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ibiti iwọ ngbé, ani ibiti ìtẹ Satani wà: ati pe iwọ dì orukọ mi mu ṣinṣin, ti iwọ kò si sẹ́ igbagbọ́ mi, li ọjọ wọnni ninu eyi ti Antipa iṣe olõtọ ajẹrikú mi, ẹniti nwọn pa ninu nyin, nibiti Satani ngbé. 14 Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere. 15 Bẹ̃ni iwọ si ní awọn ti o gbà ẹkọ awọn Nikolaitani pẹlu, ohun ti mo korira. 16 Ronupiwada; bikoṣe bẹ̃ emi ó tọ̀ ọ wá nisisiyi, emi o si fi idà ẹnu mi ba wọn jà. 17 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ́ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe ẹniti o gbà a.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Tiatira

18 Ati si angẹli ijọ ni Tiatira kọwe: Nkan wọnyi li Ọmọ Ọlọrun wi, ẹniti o ni oju rẹ̀ bi ọwọ́ iná, ti ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara; 19 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ́, ati ìsin, ati sũru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin jù ti iṣaju lọ. 20 Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa. 21 Emi si fi sã fun u lati ronupiwada; kò si fẹ ronupiwada agbere rẹ̀. 22 Kiyesi i, emi ó gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti mba a ṣe panṣaga li emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi nwọn ba ronupiwada iṣẹ wọn. 23 Emi o si fi ikú pa awọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ijọ ni yio si mọ̀ pe, emi li ẹniti nwadi inu ati ọkàn: emi o si fifun olukuluku nyin gẹgẹ bi iṣẹ nyin. 24 Ṣugbọn ẹnyin ni mo nsọ fun, ẹnyin iyokù ti mbẹ ni Tiatira, gbogbo ẹnyin ti kò ni ẹkọ́ yi, ti kò mọ̀ ohun ijinlẹ Satani (bi nwọn ti nwi), emi kò dì ẹrù miran rù nyin. 25 Ṣugbọn eyi ti ẹnyin ni, ẹ di i mu ṣinṣin titi emi o fi de. 26 Ẹniti o ba si ṣẹgun, ati ẹniti o ba pa iṣẹ mi mọ́ titi de opin, emi o fun u li aṣẹ lori awọn orilẹ-ède: 27 On o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn; bi ã ti ifọ́ ohun elo amọ̀koko li a o fọ́ wọn tũtu: bi emi pẹlu ti gba lati ọdọ Baba mi. 28 Emi o si fi irawọ owurọ̀ fun u. 29 Ẹniti o ba li eti, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmi nsọ fun awọn ijọ.

Ifihàn 3

Iṣẹ́ sí Ìjọ Sadi

1 ATI si angẹli ijọ ni Sardi kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni Ẹmí meje Ọlọrun, ati irawọ meje nì wipe; Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati pe iwọ ni orukọ pe iwọ mbẹ lãye, ṣugbọn iwọ kú. 2 Mã ṣọra, ki o si fi ẹsẹ ohun ti o kù mulẹ, ti o ṣe tan lati kú: nitori emi kò ri iṣẹ rẹ ni pipé niwaju Ọlọrun. 3 Nitorina ranti bi iwọ ti gbà, ati bi iwọ ti gbọ́, ki o si pa a mọ, ki o si ronupiwada. Njẹ, bi iwọ kò ba ṣọra, emi o de si ọ bi olè, iwọ kì yio si mọ̀ wakati ti emi o de si ọ. 4 Iwọ ni orukọ diẹ ni Sardi, ti kò fi aṣọ wọn yi ẽri; nwọn o si mã ba mi rìn li aṣọ funfun: nitori nwọn yẹ. 5 Ẹniti o ba ṣẹgun, on na li a o fi aṣọ funfun wọ̀; emi kì yio pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro ninu iwe ìye, ṣugbọn emi o jẹwọ orukọ rẹ̀ niwaju Baba mi, ati niwaju awọn angẹli rẹ̀. 6 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Filadẹfia

7 Ati si angẹli ijọ ni Filadelfia kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o jẹ mimọ́ ni wi, ẹniti iṣe olõtọ, ẹniti o ni kọkọrọ Dafidi, ẹniti o ṣí, ti kò si ẹniti yio tì; ẹniti o si tì, ti kò si ẹniti yio ṣí. 8 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ: kiyesi i, mo gbé ilẹkun ti o sí kalẹ niwaju rẹ, ti kò si ẹniti o le tì ì: pe iwọ li agbara diẹ, iwọ si pa ọ̀rọ mi mọ́, iwọ kò si sẹ́ orukọ mi. 9 Kiyesi i, emi o mú awọn ti sinagogu Satani, awọn ti nwọn nwipe Ju li awọn, ti nwọn kì si iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn nṣeke; kiyesi i, emi o mu ki nwọn wá wolẹ niwaju ẹsẹ rẹ, ki nwọn si mọ pe emi ti fẹ ọ. 10 Nitoriti iwọ ti pa ọ̀rọ sũru mi mọ́, emi pẹlu yio pa ọ mọ́ kuro ninu wakati idanwo ti mbọ̀wa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo. 11 Kiyesi i, emi mbọ̀ nisisiyi: di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rẹ. 12 Ẹniti o ba ṣẹgun, on li emi o fi ṣe ọwọ̀n ninu tẹmpili Ọlọrun mi, on kì yio si jade kuro nibẹ mọ́: emi o si kọ orukọ Ọlọrun mi si i lara, ati orukọ ilu Ọlọrun mi, ti iṣe Jerusalemu titun, ti o nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun mi wá, ati orukọ titun ti emi tikarami. 13 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Laodikia

14 Ati si angẹli ijọ ni Laodikea kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti ijẹ Amin wi, ẹlẹri olododo ati olõtọ, olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun. 15 Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, pe iwọ kò gbóna bẹ̃ni iwọ kò tutù: emi iba fẹ pe ki iwọ kuku tutù, tabi ki iwọ kuku gbóna. 16 Njẹ nitoriti iwọ ṣe ìlọ́wọwọ, ti o kò si gbóna, bẹni o kò tutù, emi o pọ̀ ọ jade kuro li ẹnu mi. 17 Nitoriti iwọ wipe, Emi li ọrọ̀, emi si npọ̀ si i li ọrọ̀, emi kò si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ kò si mọ̀ pe, òṣi ni iwọ, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni-ìhoho: 18 Emi fun ọ ni ìmọran pe ki o rà wura lọwọ mi ti a ti dà ninu iná, ki iwọ ki o le di ọlọ́rọ̀; ati aṣọ funfun, ki iwọ ki o le fi wọ ara rẹ, ati ki itiju ìhoho rẹ ki o má bã hàn, ki o si fi õgùn kùn oju rẹ, ki iwọ ki o le riran. 19 Gbogbo awọn ti emi ba fẹ ni mo mbawi, ti mo si nnà: nitorina ni itara, ki o si ronupiwada. 20 Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun, bi ẹnikẹni ba gbọ́ ohùn mi, ti o si ṣí ilẹkun, emi o si wọle tọ̀ ọ wá, emi o si ma ba a jẹun, ati on pẹlu mi. 21 Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fifun lati joko pẹlu mi lori itẹ́ mi, bi emi pẹlu ti ṣẹgun, ti mo si joko pẹlu Baba mi lori itẹ́ rẹ̀. 22 Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.

Ifihàn 4

Ìsìn ní Ọ̀run

1 LẸHIN nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan ṣí silẹ li ọrun: ohùn kini ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọ̀rọ, ti o wipe, Goke wa ìhin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ. 2 Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na. 3 Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo. 4 Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn. 5 Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun. 6 Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin. 7 Ẹda ikini si dabi kiniun, ẹda keji si dabi ọmọ malu, ẹda kẹta si ni oju bi ti enia, ẹda kẹrin si dabi idì ti nfò. 8 Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ́ mẹfa, kun fun oju yika ati ninu: nwọn kò si simi li ọsán ati li oru, wipe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ti o ti wà, ti o si mbẹ, ti o si mbọ̀wá. 9 Nigbati awọn ẹda alãye na ba si fi ogo ati ọlá ati ọpẹ́ fun ẹniti o joko lori itẹ́, ti o mbẹ lãye lai ati lailai, 10 Awọn àgba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹniti o joko lori itẹ́, nwọn a si tẹriba fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai, nwọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ́ na, wipe, 11 Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn.

Ifihàn 5

Ìwé Kíká ati Ọ̀dọ́ Aguntan

1 MO si ri li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na, iwe kan ti a kọ ninu ati lẹhin, ti a si fi èdidi meje dì. 2 Mo si ri angẹli alagbara kan, o nfi ohùn rara kede pe, Tali o yẹ lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀? 3 Kò si si ẹnikan li ọrun, tabi lori ilẹ aiye, tabi nisalẹ ilẹ, ti o le ṣí iwe na, tabi ti o le wò inu rẹ̀. 4 Emi si sọkun gidigidi, nitoriti a kò ri ẹnikan ti o yẹ lati ṣí ati lati kà iwe na, tabi lati wò inu rẹ̀. 5 Ọkan ninu awọn àgba na si wi fun mi pe, Máṣe sọkun: kiyesi i, Kiniun ẹ̀ya Juda, Gbòngbo Dafidi, ti bori lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀ mejẽje. 6 Mo si ri li arin itẹ́ na, ati awọn ẹda alãye mẹrin na, ati li arin awọn àgba na, Ọdọ-Agutan kan duro bi eyiti a ti pa, o ni iwo meje ati oju meje, ti iṣe Ẹmí meje ti Ọlọrun, ti a rán jade lọ si ori ilẹ aiye gbogbo. 7 O si wá, o si gbà a li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na. 8 Nigbati o si gbà iwe na, awọn ẹda alãye mẹrin na, ati awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ niwaju Ọdọ-Agutan na, olukuluku nwọn ní dùru ati ago wura ti o kún fun turari ti iṣe adura awọn enia mimọ́. 9 Nwọn si nkọ orin titun kan, wipe, Iwọ li o yẹ lati gbà iwe na, ati lati ṣí èdidi rẹ̀: nitoriti a ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹ̀jẹ rẹ ṣe ìrapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo, ati orilẹ-ède gbogbo wá; 10 Iwọ si ti ṣe wọn li ọba ati alufa si Ọlọrun wa: nwọn si njọba lori ilẹ aiye. 11 Emi si wò, mo si gbọ́ ohùn awọn angẹli pupọ̀ yi itẹ́ na ká, ati yi awọn ẹda alãye na ati awọn àgba na ká: iye wọn si jẹ ẹgbãrun ọna ẹgbãrun ati ẹgbẹgbẹ̀run ọna ẹgbẹgbẹ̀run; 12 Nwọn nwi li ohùn rara pe, Yiyẹ li Ọdọ-Agutan na ti a ti pa, lati gbà agbara, ati ọrọ̀, ati ọgbọ́n, ati ipá, ati ọlá, ati ogo, ati ibukún. 13 Gbogbo ẹda ti o si mbẹ li ọrun, ati lori ilẹ aiye, ati nisalẹ ilẹ, ati irú awọn ti mbẹ ninu okun, ati gbogbo awọn ti mbẹ ninu wọn, ni mo gbọ́ ti nwipe, Ki a fi ibukún ati ọlá, ati ogo, ati agbara, fun ẹniti o joko lori itẹ́ ati fun Ọdọ-Agutan na lai ati lailai. 14 Awọn ẹda alãye mẹrin na wipe; Amin. Awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ, nwọn si foribalẹ fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai.

Ifihàn 6

Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Mẹfa

1 EMI si ri nigbati Ọdọ-Agutan na ṣí ọ̀kan ninu èdidi wọnni, mo si gbọ́ ọ̀kan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì nwi bi ẹnipe sisan ãrá pe, Wá, wò o. 2 Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin funfun kan: ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni ọrun kan; a si fi ade kan fun u: o si jade lọ lati iṣẹgun de iṣẹgun. 3 Nigbati o si ṣí èdidi keji, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye keji nwipe, Wá, wò o. 4 Ẹṣin miran ti o pupa si jade: a si fi agbara fun ẹniti o joko lori rẹ̀, lati gbà alafia kuro lori ilẹ aiye, ati pe ki nwọn ki o mã pa ara wọn: a si fi idà nla kan le e lọwọ. 5 Nigbati o si ṣí èdidi kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹta nwipe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin dúdu kan; ẹniti o joko lori rẹ̀ ni oṣuwọn awẹ́ meji li ọwọ́ rẹ̀. 6 Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara. 7 Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o. 8 Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin rọndọnrọndọn kan: orukọ ẹniti o joko lori rẹ̀ ni Ikú, ati Ipò-okú si tọ̀ ọ lẹhin. A si fi agbara fun wọn lori idamẹrin aiye, lati fi idà, ati ebi, ati ikú, ati ẹranko ori ilẹ aiye pa. 9 Nigbati o si ṣí èdidi karun, mo ri labẹ pẹpẹ, ọkàn awọn ti a ti pa nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí ti nwọn dìmu: 10 Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye? 11 A si fi aṣọ funfun fun gbogbo wọn; a si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o simi di ìgba diẹ na, titi iye awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ ati arakunrin wọn ti a o pa bi wọn, yio fi pé. 12 Nigbati o si ṣí èdidi kẹfa mo si ri, si kiyesi i, ìṣẹlẹ nla kan ṣẹ̀; õrùn si dudu bi aṣọ-ọfọ onirun, oṣupa si dabi ẹ̀jẹ; 13 Awọn irawọ oju ọrun si ṣubu silẹ gẹgẹ bi igi ọpọtọ iti rẹ̀ àigbó eso rẹ̀ dànu, nigbati ẹfũfu nla ba mì i. 14 A si ká ọ̀run kuro bi iwe ti a ká; ati olukuluku oke ati erekuṣu li a si ṣí kuro ni ipò wọn. 15 Awọn ọba aiye ati awọn ọlọlá ati awọn olori ogun, ati awọn ọlọrọ̀ ati awọn alagbara, ati olukuluku ẹrú, ati olukuluku omnira, si fi ara wọn pamọ́ ninu ihò-ilẹ, ati ninu àpata ori òke: 16 Nwọn si nwi fun awọn òke ati awọn àpata na pe, Ẹ wólu wa, ki ẹ si fi wa pamọ́ kuro loju ẹniti o joko lori itẹ́, ati kuro ninu ibinu Ọdọ-Agutan na: 17 Nitori ọjọ nla ibinu wọn de; tani si le duro?

Ifihàn 7

Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan Israẹli

1 LẸHIN eyi ni mo ri angẹli mẹrin duro ni igun mẹrẹrin aiye, nwọn di afẹfẹ mẹrẹrin aiye mu, ki o máṣe fẹ́ sori ilẹ, tabi sori okun, tabi sara igikigi. 2 Mo si ri angẹli miran ti o nti ìha ìla-õrùn goke wá, ti on ti èdidi Ọlọrun alãye lọwọ: o si kigbe li ohùn rara si awọn angẹli mẹrin na ti a fifun lati pa aiye ati okun lara, 3 Wipe, Ẹ máṣe pa aiye, tabi okun, tabi igi lara, titi awa o fi fi èdidi sami si awọn iranṣẹ Ọlọrun wa ni iwaju wọn. 4 Mo si gbọ́ iye awọn ẹniti a fi èdidi sami si: awọn ti a sami si jẹ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji lati inu gbogbo ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli wá. 5 Lati inu ẹ̀ya Juda a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Reubeni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Gadi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. 6 Lati inu ẹ̀ya Aṣeri a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Neftalimu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Manasse a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. 7 Lati inu ẹ̀ya Simeoni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Lefi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Issakari a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. 8 Lati inu ẹ̀ya Sebuloni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Josefu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Benjamini a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.

Àwọn Aṣẹ́gun láti Gbogbo Orílẹ̀-Èdè

9 Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn; 10 Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ́, ati ti Ọdọ-Agutan. 11 Gbogbo awọn angẹli si duro yi itẹ́ na ká, ati yi awọn àgba ati awọn ẹda alãye mẹrin na ká, nwọn wolẹ nwọn si dojubolẹ niwaju itẹ́ na nwọn si sìn Ọlọrun, 12 Wipe, Amin: Ibukún, ati ogo, ati ọgbọ́n, ati ọpẹ́, ati agbara, ati ipá fun Ọlọrun wa lai ati lailai. Amin. 13 Ọkan ninu awọn àgba na si dahùn, o bi mi pe, Tali awọn wọnyi ti a wọ̀ li aṣọ funfun nì? nibo ni nwọn si ti wá? 14 Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na. 15 Nitorina ni nwọn ṣe mbẹ niwaju itẹ́ Ọlọrun, ti nwọn si nsìn i li ọsán ati li oru ninu tẹmpili rẹ̀: ẹniti o joko lori itẹ́ na yio si ṣiji bò wọn. 16 Ebi kì yio pa wọn mọ́, bẹ̃li ongbẹ kì yio gbẹ wọn mọ́; bẹ̃li õrùn kì yio pa wọn tabi õrukõru. 17 Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ́ na ni yio mã ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yio si mã ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iyè: Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.

Ifihàn 8

Ọ̀dọ́ Aguntan Tú Èdìdì Keje

1 NIGBATI o si ṣí èdidi keje, kẹ́kẹ́ pa li ọrun niwọn àbọ wakati kan. 2 Mo si ri awọn angẹli meje ti nwọn duro niwaju Ọlọrun; a si fi ipè meje fun wọn. 3 Angẹli miran si wá, o si duro tì pẹpẹ, o ni awo turari wura kan; a si fi turari pupọ̀ fun u, ki o le fi i kún adura gbogbo awọn enia mimọ́ lori pẹpẹ wura ti mbẹ niwaju itẹ́. 4 Ati ẹ̃fin turari na pẹlu adura awọn enia mimọ́ si gòke lọ siwaju Ọlọrun lati ọwọ́ angẹli na wá. 5 Angeli na si mu awo turari na, o si fọ̀n iná ori pẹpẹ kun u, o si dà a sori ilẹ aiye: a si gbọ ohùn, ãra si san, mànamána si kọ, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀.

Àwọn Kàkàkí Mẹfa

6 Awọn angẹli meje na ti nwọn ni ipè meje si mura lati fun wọn. 7 Ekini si fun, yinyín ati iná ti o dàpọ̀ pẹlu ẹ̀jẹ si jade, a si dà wọn sori ilẹ aiye: idamẹta ilẹ aiye si jóna, idamẹta awọn igi si jóna, ati gbogbo koriko tutù si jóna. 8 Angẹli keji si fun, a si wọ́ ohun kan bi òke nla ti njona sọ sinu okun: idamẹta okun si di ẹ̀jẹ; 9 Ati idamẹta awọn ẹda ti mbẹ ninu okun ti o ni ẹmí si kú; ati idamẹta awọn ọkọ̀ si bajẹ. 10 Angẹli kẹta si fun, irawọ̀ nla kan ti njo bi fitila si bọ́ lati ọrun wá, o si bọ sori idamẹta awọn odo ṣiṣàn, ati sori awọn orisun omi; 11 A si npè orukọ irawọ na ni Iwọ idamẹta awọn omi si di iwọ, ọ̀pọlọpọ enia si ti ipa awọn omi na kú, nitoriti a sọ wọn di kikorò. 12 Angẹli kẹrin si fun, a si kọlu idamẹta õrùn, ati idamẹta oṣupa, ati idamẹta awọn irawọ, ki idamẹta wọn le ṣõkun, ki ọjọ maṣe mọlẹ fun idamẹta rẹ̀, ati oru bakanna. 13 Mo si wò, mo si gbọ́ idì kan ti nfò li ãrin ọrun, o nwi li ohùn rara pe, Egbé, egbé, egbé, fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye nitori ohùn ipè iyoku ti awọn angẹli mẹta ti mbọwá fun.

Ifihàn 9

1 ANGẸLI karun si fun, mo si ri irawọ kan bọ́ si ilẹ lati ọrun wá: a si fi iṣika iho ọgbun fun u. 2 O si ṣí iho ọgbun na; ẹ̃fin si ru jade lati inu iho na wá, bi ẹ̃fin ileru nla; õrùn ati oju sanma si ṣõkun nitori ẹ̃fin iho na. 3 Ẽṣú si jade ti inu ẹ̃fin na wá sori ilẹ: a si fi agbara fun wọn bi akẽkẽ ilẹ ti li agbara. 4 A si sọ fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe pa koriko ilẹ lara, tabi ohun tutù kan, tabi igikigi kan; bikoṣe awọn enia ti kò ni èdidi Ọlọrun ni iwaju wọn. 5 A si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe pa wọn, ṣugbọn ki a dá wọn li oró li oṣù marun: oró wọn si dabi oró akẽkẽ, nigbati o ba ta enia. 6 Li ọjọ wọnni li awọn enia yio si mã wá ikú, nwọn kì yio si ri i; nwọn o si fẹ lati kú, ikú yio si sá kuro lọdọ wọn. 7 Iré awọn ẽṣú na si dabi awọn ẹṣin ti a mura silẹ fun ogun; ati li ori wọn ni bi ẹnipe awọn ade ti o dabi wura wà, oju wọn si dabi oju enia; 8 Nwọn si ni irun bi irun obinrin, ehin wọn si dabi ti kiniun. 9 Nwọn si ni awo ìgbàiya, bi awo ìgbàiya irin; iró iyẹ́ wọn si dabi iró kẹkẹ́ ẹṣin pupọ̀ ti nsúré lọ si ogun. 10 Nwọn si ni ìru ati oró bi ti akẽkẽ, ati ni ìru wọn ni agbara wọn wà lati pa enia lara fun oṣù marun. 11 Nwọn ni angẹli ọgbun na bi ọba lori wọn, orukọ rẹ̀ li ede Heberu ni Abaddoni, ati li ède Griki orukọ rẹ̀ amã jẹ Apollioni. 12 Egbé kan kọja; kiyesi i, egbé meji mbọ̀ sibẹ lẹhin eyi. 13 Angẹli kẹfa si fun, mo si gbọ́ ohùn kan lati ibi iwo mẹrin pẹpẹ wura wá, ti mbẹ niwaju Ọlọrun, 14 Nwi fun angẹli kẹfa na ti o ni ipè na pe, Tú awọn angẹli mẹrin nì silẹ ti a dè lẹba odò nla Eufrate. 15 A si tú awọn angẹli mẹrin na silẹ, ti a ti pese tẹlẹ fun wakati na, ati ọjọ na, ati oṣù na, ati ọdun na, lati pa idamẹta enia. 16 Iye ogun awọn ẹlẹṣin si jẹ ãdọta ọkẹ́ lọna igba: mo si gbọ́ iye wọn. 17 Bayi ni mo si ri awọn ẹṣin na li ojuran, ati awọn ti o gùn wọn; nwọn ni awo ìgbaiya iná, ati ti jakinti, ati ti imí ọjọ: ori awọn ẹṣin na si dabi ori awọn kiniun; ati lati ẹnu wọn ni iná, ati ẹ̃fin, ati imí ọjọ ti njade. 18 Nipa iyọnu mẹta wọnyi li a ti pa idamẹta enia, nipa iná, ati nipa, ẹ̃fin, ati nipa imí ọjọ ti o nti ẹnu wọn jade. 19 Nitoripe agbara awọn ẹṣin na mbẹ li ẹnu wọn ati ni iru wọn: nitoripe ìru wọn dabi ejò, nwọn si ni ori, awọn wọnyi ni nwọn si fi npa-ni-lara. 20 Ṣugbọn awọn enia iyokù, ti a kò si ti ipa iyọnu wọnyi pa, kò si ronupiwada iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ki nwọn ki o máṣe sìn awọn ẹmi èṣu, ati ere wura, ati ti fadaka, ati ti idẹ, ati ti okuta, ati ti igi mọ́, awọn ti kò le riran, tabi ki nwọn gbọran, tabi ki nwọn rìn: 21 Bẹ̃ni nwọn kò ronupiwada enia pipa wọn, tabi oṣó wọn, tabi àgbere wọn, tabi olè wọn.

Ifihàn 10

Angẹli ati Ìwé-kíká Kékeré

1 MO si ri angẹli miran alagbara o nti ọrun sọkalẹ wá, a fi awọsanma wọ̀ ọ li aṣọ: oṣumare si mbẹ li ori rẹ̀, oju rẹ̀ si dabi õrùn, ati ẹsẹ rẹ̀ bi ọwọ̀n iná: 2 O si ni iwe kekere kàn ti a ṣi li ọwọ́ rẹ̀: o si fi ẹsẹ rẹ̀ ọtun le okun, ati ẹsẹ rẹ̀ òsi le ilẹ, 3 O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun. 4 Nigbati awọn ãrá meje na fọhun, mo mura ati kọwe: mo si gbọ́ ohùn lati ọrun wá nwi fun mi pe, Fi èdidi dí ohun ti awọn ãrá meje na sọ, má si ṣe kọ wọn silẹ. 5 Angẹli na ti mo ri ti o duro lori okun ati lori ilẹ, si gbé ọwọ́ rẹ̀ si oke ọrun, 6 O si fi ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai búra, ẹniti o dá ọrun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ aiye, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati okun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, pe ìgba kì yio si mọ́: 7 Ṣugbọn li ọjọ ohùn angẹli keje, nigbati yio ba fun ipe, nigbana li ohun ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi ihinrere ti o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli. 8 Ohùn na ti mo gbọ́ lati ọrun wá tún mba mi sọrọ, o si wipe, Lọ, gbà iwe ti o ṣí nì lọwọ angẹli ti o duro lori okun ati lori ilẹ. 9 Mo si tọ̀ angẹli na lọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni iwe kekere nì. O si wi fun mi pe, Gbà ki o si jẹ ẹ tan; yio mu inu rẹ korò, ṣugbọn li ẹnu rẹ yio dabi oyin. 10 Mo si gbà iwe kekere na li ọwọ́ angẹli na, mo si jẹ ẹ tan; o si dùn li ẹnu mi bi oyin: bi mo si ti jẹ ẹ tan, inu mi korò. 11 A si wi fun mi pe, Iwọ o tún sọ asọtẹlẹ lori ọpọlọpọ enia, ati orilẹ, ati ède, ati awọn ọba.

Ifihàn 11

Àwọn Ẹlẹ́rìí Meji

1 A si fi ifefe kan fun mi ti ó dabi ọpá: o wipe, Dide, si wọ̀n tẹmpili Ọlọrun, ati pẹpẹ, ati awọn ti nsìn ninu rẹ̀; 2 Si fi agbala ti mbẹ lode tẹmpili silẹ, má si ṣe wọ̀n ọ; nitoriti a fi i fun awọn Keferi: ilu mimọ́ na li nwọn o si tẹ̀ mọlẹ li oṣu mejilelogoji. 3 Emi o si yọnda fun awọn ẹlẹri mi mejeji, nwọn ó si sọtẹlẹ fun ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta ninu aṣọ-ọfọ. 4 Wọnyi ni igi oróro meji nì, ati ọpá fitila meji nì, ti nduro niwaju Oluwa aiye. 5 Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a. 6 Awọn wọnyi li o ni agbara lati sé ọrun, ti ojo kò fi rọ̀ li ọjọ asọtẹlẹ wọn: nwọn si ni agbara lori omi lati sọ wọn di ẹ̀jẹ, ati lati fi oniruru ajakalẹ arun kọlu aiye, nigbakugba ti nwọn ba fẹ. 7 Nigbati nwọn ba si ti pari ẹrí wọn, ẹranko ti o nti inu ọ̀gbun goke wá ni yio ba wọn jagun, yio si ṣẹgun wọn, yio si pa wọn. 8 Okú wọn yio si wà ni igboro ilu nla nì, ti a npè ni Sodomu ati Egipti nipa ti ẹmí, nibiti a gbé kàn Oluwa wọn mọ agbelebu. 9 Ati ninu awọn enia, ati ẹya, ati ède, ati orilẹ, nwọn wo okú wọn fun ijọ mẹta on àbọ, nwọn kò si jẹ ki a gbé okú wọn sinu isà okú. 10 Ati awọn ti o ngbé ori ilẹ aiye yio si yọ̀ le wọn lori, nwọn si ṣe ariya, nwọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitoriti awọn woli mejeji yi dá awọn ti o mbẹ lori ilẹ aiye loró. 11 Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn. 12 Nwọn si gbọ́ ohùn nla kan lati ọrun wá nwi fun wọn pe, Ẹ gòke wá ìhin. Nwọn si gòke lọ si ọrun ninu awọsanma; awọn ọtá wọn si ri wọn. 13 Ni wakati na ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀, idamẹwa ilu na si wó, ati ninu ìṣẹlẹ na ẹdẹgbarin enia li a pa: ẹ̀ru si ba awọn iyokù, nwọn si fi ogo fun Ọlọrun ọrun. 14 Egbé keji kọja; si kiyesi i, egbé kẹta si mbọ̀wá kánkán.

Kàkàkí Keje

15 Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai. 16 Awọn àgba mẹrinlelogun nì ti nwọn joko niwaju Ọlọrun lori ítẹ wọn, dojubolẹ, nwọn si sìn Ọlọrun, 17 Wipe, Awa fi ọpẹ́ fun ọ, Oluwa Ọlọrun, Olodumare, ti mbẹ, ti o si ti wà, ti o si ma bọ̀; nitoriti iwọ ti gbà agbara nla rẹ, iwọ si ti jọba. 18 Inu si bi awọn orilẹ-ède, ibinu rẹ si de, ati ìgba lati dá awọn okú lẹjọ, ati lati fi ere fun awọn iranṣẹ rẹ woli ati awọn enia mimọ́ ati awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ, ati ẹni kekere ati ẹni nla; ati lati run awọn ti npa aiye run. 19 A si ṣí tẹmpili Ọlọrun silẹ li ọrun, a si ri apoti majẹmu ninu tẹmpili rẹ̀: mànamána si kọ, a si gbọ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀, yinyín nla si bọ.

Ifihàn 12

Obinrin kan ati Ẹranko Ewèlè

1 ÀMI nla kan si hàn li ọrun; obinrin kan ti a fi õrùn wọ̀ li aṣọ, oṣupa si mbẹ labẹ ẹsẹ rẹ̀, ade onirawọ mejila si mbẹ li ori rẹ̀: 2 O si lóyun, o si kigbe ni irọbi, o si wà ni irora ati bimọ. 3 Àmi miran si hàn li ọrun; si kiyesi i, dragoni pupa nla kan, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati adé meje li ori rẹ̀. 4 Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o si ju wọn si ilẹ aiye, dragoni na si duro niwaju obinrin na ti o fẹ bímọ, pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ. 5 O si bí ọmọkunrin kan ti yio fi ọpá irin ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀. 6 Obinrin na si sá lọ si aginjù, nibiti a gbé ti pèse àye silẹ dè e lati ọwọ́ Ọlọrun wá, pe ki nwọn ki o mã bọ́ ọ nibẹ̀ li ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta. 7 Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀. 8 Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun. 9 A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀. 10 Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru. 11 Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú. 12 Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru ṣá li on ni. 13 Nigbati dragoni na ri pe a lé on lọ si ilẹ aiye, o ṣe inunibini si obinrin ti o bí ọmọkunrin na. 14 A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na. 15 Ejò na si tú omi jade lati ẹnu rẹ̀ wá bi odo nla sẹhin obinrin na, ki o le mu ki ìṣan omi na gbá a lọ. 16 Ilẹ si ràn obinrin na lọwọ, ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si fi ìṣan omi na mu, ti dragoni na tú jade lati ẹnu rẹ̀ wá. 17 Dragoni na si binu gidigidi si obinrin na, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyokù jagun, ti nwọn npa ofin Ọlọrun mọ́, ti nwọn si di ẹrí Jesu mu.

Ifihàn 13

Àwọn Ẹranko Meji

1 O si duro lori iyanrìn okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá, o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀ na ni orukọ ọrọ-odi. 2 Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀ si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla. 3 Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ̀ bi ẹnipe a sá a pa, a si ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ̀ na san, gbogbo aiye si fi iyanu tẹle ẹranko na. 4 Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? tali o si le ba a jagun? 5 A si fun u li ẹnu lati mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu mejilelogoji. 6 O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun. 7 A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ. 8 Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye. 9 Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́. 10 Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ́ awọn enia mimọ́ gbé wà. 11 Mo si ri ẹranko miran goke lati inu ilẹ wá; o si ni iwo meji bi ọdọ-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni. 12 O si nlò gbogbo agbara ẹranko ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san. 13 O si nṣe ohun iyanu nla, ani ti o fi nmu iná sọkalẹ lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia. 14 O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè. 15 A si fi fun u lati fi ẹmí fun aworan ẹranko na ki o mã sọ̀rọ, ki o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na. 16 O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ̀ ati talakà, omnira ati ẹrú, ki a fi àmi kan fun wọn li ọwọ́ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn: 17 Ati ki ẹnikẹni má le rà tabi ki o tà, bikoṣe ẹniti o bá ni ami orukọ ẹranko na, tabi iye orukọ rẹ̀. 18 Nihin ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹniti o ba ni oye, ki o ṣiro iye ti mbẹ lara ẹranko na: nitori iye enia ni; iye rẹ̀ na si jẹ ọ̀talelẹgbẹta o le mẹfa.

Ifihàn 14

Orin Àwọn Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan

1 Mo si wò, si kiyesi i, Ọdọ-Agutan na duro lori òke Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, nwọn ni orukọ rẹ̀, ati orukọ Baba rẹ̀ ti a kọ si iwaju wọn. 2 Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá, bi ariwo omi pupọ̀, ati bi sisán ãrá nla: mo si gbọ́ awọn aludùru, nwọn nlù dùru wọn: 3 Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá. 4 Awọn wọnyi li a kò fi obinrin sọ di ẽri; nitoripe wundia ni nwọn. Awọn wọnyi ni ntọ̀ Ọdọ-Agutan na lẹhin nibikibi ti o ba nlọ. Awọn wọnyi li a rà pada lati inu awọn enia wá, nwọn jẹ́ akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan na. 5 A kò si ri eke li ẹnu wọn, nwọn jẹ alailabuku.

Iṣẹ́ tí Àwọn Angẹli Mẹta Jẹ́

6 Mo si ri angẹli miran nfò li agbedemeji ọrun, ti on ti ihinrere ainipẹkun lati wãsu fun awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, ati fun gbogbo orilẹ, ati ẹya, ati ède, ati enia, 7 O nwi li ohùn rara pe, Ẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun u; nitoriti wakati idajọ rẹ̀ de: ẹ si foribalẹ fun ẹniti o dá ọrun, on aiye, ati okun, ati awọn orisun omi. 8 Angẹli miran si tẹ̀le e, o nwipe, Babiloni wó, Babiloni ti o tobi nì wó, eyiti o ti nmú gbogbo orilẹ-ède mu ninu ọti-waini ibinu àgbere rẹ̀. 9 Angẹli kẹta si tẹle wọn, o nwi li ohùn rara pe, Bi ẹnikẹni ba nforibalẹ fun ẹranko nì, ati aworan rẹ̀, ti o si gbà àmi si iwaju rẹ̀ tabi si ọwọ́-rẹ̀, 10 On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rẹ̀; a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan: 11 Ẹ̃fin oró wọn si nlọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru, awọn ti nforibalẹ fun ẹranko na ati fun aworan rẹ̀, ati ẹnikẹni ti o ba si gbà àmi orukọ rẹ̀. 12 Nihin ni sũru awọn enia mimọ́ gbé wà: awọn ti npa ofin Ọlọrun ati igbagbọ́ Jesu mọ́. 13 Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá nwi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Alabukún fun li awọn okú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhin lọ: Bẹni, li Ẹmí wi, ki nwọn ki o le simi kuro ninu lãlã wọn, nitori iṣẹ wọn ntọ̀ wọn lẹhin.

Ìkórè Ayé

14 Mo si wò, si kiyesi i, awọsanma funfun kan, ati lori awọsanma na ẹnikan joko ti o dabi Ọmọ-enia, ti on ti ade wura li ori rẹ̀, ati dòjé mimú li ọwọ́ rẹ̀. 15 Angẹli miran si ti inu tẹmpili jade wá ti nke li ohùn rara si ẹniti o joko lori awọsanma pe, Tẹ̀ doje rẹ bọ̀ ọ, ki o si mã kore: nitori akokò ati kore de, nitori ikorè aiye ti gbó tan. 16 Ẹniti o joko lori awọsanma na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ori ilẹ aiye; a si ṣe ikore ilẹ aiye. 17 Angẹli miran si ti inu tẹmpili ti mbẹ li ọrun jade wá, ti on ti doje mimu. 18 Angẹli miran si ti ibi pẹpẹ jade wá, ti o ni agbara lori iná; o si ke li ohùn rara si ẹniti o ni doje mimu, wipe, Tẹ̀ doje rẹ mimu bọ̀ ọ, ki o si rẹ́ awọn idi ajara aiye, nitori awọn eso rẹ̀ ti pọ́n. 19 Angẹli na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ilẹ aiye, o si ké ajara ilẹ aiye, o si kó o lọ sinu ifúnti, ifúnti nla ibinu Ọlọrun. 20 A si tẹ̀ ifúnti na lẹhin odi ilu na, ẹ̀jẹ si ti inu ifúnti na jade, ani ti o tó okùn ijanu ẹṣin jinna to ẹgbẹjọ furlongi.

Ifihàn 15

Àwọn Angẹli tí Ó Mú Àjàkálẹ̀ Àrùn Ìkẹyìn Wá

1 MO si ri àmi miran li ọrun ti o tobi ti o si yanilẹnu, awọn angẹli meje ti o ni awọn iyọnu meje ikẹhin, nitori ninu wọn ni ibinu Ọlọrun de opin. 2 Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun. 3 Nwọn si nkọ orin ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ati orin ti Ọdọ-Agutan, wipe, Titobi ati iyanu ni awọn iṣẹ rẹ, Oluwa Ọlọrun Olodumare; ododo ati otitọ li ọ̀na rẹ, iwọ Ọba awọn orilẹ-ede. 4 Tani kì yio bẹ̀ru, Oluwa, ti kì yio si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mimọ́: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio si wá, ti yio si foribalẹ niwaju rẹ; nitori a ti fi idajọ rẹ hàn. 5 Lẹhin na mo si wò, si kiyesi i, a ṣí tẹmpili agọ́ ẹrí li ọrun silẹ: 6 Awọn angẹli meje na si ti inu tẹmpili jade wá, nwọn ni iyọnu meje nì, a wọ̀ wọn li aṣọ ọgbọ funfun ti ndan, a si fi àmure wura dì wọn li õkan àiya. 7 Ati ọkan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì fi ìgo wura meje fun awọn angẹli meje na, ti o kún fun ibinu Ọlọrun, ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai. 8 Tẹmpili na si kún fun ẹ̃fin lati inu ogo Ọlọrun ati agbara rẹ̀ wá; ẹnikẹni kò si le wọ̀ inu tẹmpili na lọ titi a fi mu iyọnu mejeje awọn angẹli meje na ṣẹ.

Ifihàn 16

Àwọn Àwo tí Ó Kún fún Ibinu Ọlọrun

1 MO si gbọ́ ohùn nla kan lati inu tẹmpili wá, nwi fun awọn angẹli meje nì pe, Ẹ lọ, ẹ si tú ìgo ibinu Ọlọrun wọnni si ori ilẹ aiye. 2 Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀. 3 Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun. 4 Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ. 5 Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi. 6 Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn. 7 Mo si gbọ́ pẹpẹ nke wipe, Bẹ̃ni, Oluwa Ọlọrun Olodumare, otitọ ati ododo ni idajọ rẹ. 8 Ẹkẹrin si tú ìgo tirẹ̀ sori õrùn; a si yọnda fun u lati fi iná jó enia lara. 9 A si fi õru nla jo awọn enia lara, nwọn si sọ̀rọ-òdi si orukọ Ọlọrun, ẹniti o li agbara lori iyọnu wọnyi: nwọn kò si ronupiwada lati fi ogo fun u. 10 Ẹkarun si tu ìgo tirẹ̀ sori ìtẹ ẹranko na; ilẹ-ọba rẹ̀ si ṣokunkun; nwọn si nge ahọn wọn jẹ nitori irora. 11 Nwọn si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ọrun nitori irora wọn ati nitori egbò wọn, nwọn kò si ronupiwada iṣẹ wọn. 12 Ẹkẹfa si tú ìgo tirẹ̀ sori odò nla Eufrate; omi rẹ̀ si gbẹ, ki a le pese ọna fun awọn ọba ati ìla-õrùn wá. 13 Mo si ri awọn ẹmí aimọ́ mẹta bi ọ̀pọlọ́, nwọn ti ẹnu dragoni na ati ẹnu ẹranko na ati ẹnu woli eke na jade wá. 14 Nitori ẹmi èṣu ni wọn, ti nṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti njade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ aiye, lati gbá wọn jọ si ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare. 15 Kiyesi i, mo mbọ̀ bi olè. Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rẹ̀ mọ́, ki o má bã rìn ni ìhoho, nwọn a si ri itiju rẹ̀. 16 O si gbá wọn jọ si ibikan ti a npè ni Har-mageddoni li ède Heberu. 17 Ekeje si tú ìgo tirẹ̀ si oju ọrun; ohùn nla kan si ti inu tẹmpili jade lati ibi itẹ́, wipe, O pari. 18 Mànamána si kọ, a si gbọ́ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, iru eyiti kò ṣẹ̀ ri lati igbati enia ti wà lori ilẹ, iru ìṣẹlẹ nla bẹ̃, ti o si lagbara tobẹ̃. 19 Ilu nla na si pin si ipa mẹta, awọn orilẹ-ède si ṣubu: Babiloni nla si wá si iranti niwaju Ọlọrun, lati fi ãgo ọti-waini ti irunu ibinu rẹ̀ fun u. 20 Olukuluku erekuṣu si salọ, a kò si ri awọn òke nla mọ́. 21 Yinyín nla, ti ọkọ̃kan rẹ̀ to talenti ni ìwọ̀n, si bọ́ lù awọn enia lati ọrun wà: awọn enia si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun nitori iyọnu yinyín na; nitoriti iyọnu rẹ̀ na pọ̀ gidigidi.

Ifihàn 17

Babiloni Ìlú Ńlá, Gbajúmọ̀ Àgbèrè

1 ỌKAN ninu awọn angẹli meje na ti o ni ìgo meje wọnni si wá, o si ba mi sọrọ wipe, Wá nihin; emi o si fi idajọ àgbere nla nì ti o joko lori omi pupọ̀ han ọ: 2 Ẹniti awọn ọba aiye ba ṣe àgbere, ti a si ti fi ọti-waini àgbere rẹ̀ pa awọn ti ngbe inu aiye. 3 O si gbe mi ninu Ẹmí lọ si aginjù: mo si ri obinrin kan o joko lori ẹranko alawọ̀ odòdó kan ti o kún fun orukọ ọrọ-odi, o ni ori meje ati iwo mẹwa. 4 A si fi aṣọ elese aluko ati aṣọ odòdó wọ obinrin na, a si fi wura ati okuta iyebiye ati perli ṣe e lọṣọ́, o ni ago wura kan li ọwọ́ rẹ̀, ti o kún fun irira ati fun ẹgbin àgbere rẹ̀: 5 Ati niwaju rẹ̀ ni orukọ kan ti a kọ, OHUN IJINLẸ, BABILONI NLA, IYA AWỌN PANṢAGA ATI AWỌN OHUN IRIRA AIYE. 6 Mo si ri obinrin na mu ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́, ati ẹ̀jẹ awọn ajẹrikú Jesu li amuyo: nigbati mo si ri i, ẹnu yà mi gidigidi. 7 Angẹli si wi fun mi pe, Nitori kili ẹnu ṣe yà ọ? emi o sọ ti ijinlẹ obinrin na fun ọ, ati ti ẹranko ti o gùn, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa. 8 Ẹranko ti iwọ ri nì, o ti wà, kò si sí mọ́: yio si ti inu ọgbun gòke wá, yio si lọ sinu egbé: ẹnu yio si yà awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, orukọ awọn ẹniti a kò ti kọ sinu iwe ìye lati ipilẹṣẹ aiye, nigbati nwọn nwò ẹranko ti o ti wà, ti kò si sí mọ́, ti o si mbọ̀wá. 9 Nihin ní itumọ ti o li ọgbọ́n wà. Ori meje nì oke nla meje ni, lori eyi ti obinrin na joko. 10 Ọba meje si ni nwọn: awọn marun ṣubu, ọkan mbẹ, ọkan iyokù kò si ti ide; nigbati o ba si de, yio duro fun igba kukuru. 11 Ẹranko ti o si ti wà, ti kò si si, on na si ni ẹkẹjọ, o si ti inu awọn meje na wá, o si lọ si iparun. 12 Iwo mẹwa ti iwọ si ri nì ọba mẹwa ni nwọn, ti nwọn kò iti gba ijọba; ṣugbọn nwọn gba ọla bi ọba pẹlu ẹranko na fun wakati kan. 13 Awọn wọnyi ni inu kan, nwọn o si fi agbara ati ọla wọn fun ẹranko na. 14 Awọn wọnyi ni yio si mã ba Ọdọ-Agutan jagun, Ọdọ-Agutan na yio si ṣẹgun wọn: nitori on ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn ti o si wà pẹlu rẹ̀, ti a pè, ti a yàn, ti nwọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu. 15 O si wi fun mi pe, Awọn omi ti iwọ ri nì, nibiti àgbere nì joko, awọn enia ati ẹya ati orilẹ ati oniruru ède ni wọn. 16 Ati iwo mẹwa ti iwọ ri, ati ẹranko na, awọn wọnyi ni yio korira àgbere na, nwọn o si sọ ọ di ahoro ati ẹni ìhoho, nwọn o si jẹ ẹran ara rẹ̀, nwọn o si fi iná sun u patapata. 17 Nitori Ọlọrun ti fi sinu ọkàn wọn lati mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ, lati ni inu kan, ati lati fi ijọba wọn fun ẹranko na, titi ọ̀rọ Ọlọrun yio fi ṣẹ. 18 Obinrin ti iwọ ri ni ilu nla nì, ti njọba lori awọn ọba ilẹ aiye.

Ifihàn 18

Babiloni tú

1 LẸHIN nkan wọnyi mo si ri angẹli miran, o nti ọrun sọkalẹ wá ti on ti agbara nla; ilẹ aiye si ti ipa ogo rẹ̀ mọlẹ. 2 O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira. 3 Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀. 4 Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀. 5 Nitori awọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gá ani de ọrun, Ọlọrun si ti ranti aiṣedẽdẽ rẹ̀. 6 San a fun u, ani bi on ti san fun-ni, ki o si ṣe e ni ilọpo meji fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: ninu ago na ti o ti kùn, on ni ki ẹ si kún fun u ni meji. 7 Niwọn bi o ti yin ara rẹ̀ logo to, ti o si huwa wọbia, niwọn bẹ̃ ni ki ẹ da a loro ki ẹ si fún u ni ibanujẹ: nitoriti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, mo joko bi ọbabirin, emi kì si iṣe opó, emi ki yio si ri ibinujẹ lai. 8 Nitorina ni ijọ kan ni iyọnu rẹ̀ yio de, ikú, ati ibinujẹ, ati ìyan; a o si fi iná sun u patapata: nitoripe alagbara ni Oluwa Ọlọrun ti nṣe idajọ rẹ̀. 9 Ati awọn ọba aiye, ti o ti mba a ṣe àgbere, ti nwọn si mba a hu iwà wọbia, yio si pohùnrere ẹkún le e lori, nigbati nwọn ba wo ẹ̃fin ijona rẹ̀. 10 Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de. 11 Awọn oniṣowo aiye si nsọkun, nwọn si nṣọ̀fọ lori rẹ̀; nitoripe ẹnikẹni kò rà ọjà wọn mọ́: 12 Ọjà wura, ati ti fadaka, ati ti okuta iyebiye, ati ti perli, ati ti aṣọ ọgbọ wíwe, ati ti elese aluko, ati ti ṣẹ́dà, ati ti ododó, ati ti gbogbo igi olõrun didun, ati ti olukuluku ohun èlo ti ehin-erin, ati ti olukuluku ohun èlo ti a fi igi iyebiye ṣe, ati ti idẹ, ati ti irin, ati ti okuta marbili, 13 Ati ti kinamoni, ati ti oniruru ohun olõrun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti ọti-waini, ati ti oróro, ati ti iyẹfun daradara, ati ti alikama, ati ti ẹranlá, ati ti agutan, ati ti ẹṣin, ati ti kẹkẹ́, ati ti ẹrú, ati ti ọkàn enìa. 14 Ati awọn eso ti ọkàn rẹ nṣe ifẹkufẹ si, sì lọ kuro lọdọ rẹ, ati ohun gbogbo ti o dùn ti o si dara ṣegbe mọ ọ loju, a kì yio si tún ri wọn mọ́ lai. 15 Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ, 16 Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli! 17 Nitoripe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹ̃ di asan. Ati olukuluku olori ọkọ̀, ati olukuluku ẹniti nrin oju omi lọ si ibikibi, ati awọn ti nṣiṣẹ, ninu ọkọ̀, ati awọn ti nṣowo oju okun duro li òkere rére, 18 Nwọn si kigbe nigbati nwọn ri ẹ̃fin jijona rẹ̀, wipe, Ilu wo li o dabi ilu nla yi? 19 Nwọn si kù ekuru si ori wọn, nwọn kigbe, nwọn sọkun, nwọn si nṣọfọ, wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, ninu eyi ti a sọ gbogbo awọn ti o ni ọkọ̀ li okun di ọlọrọ̀ nipa ohun iyebiye rẹ̀! nitoripe ni wakati kan a sọ ọ di ahoro. 20 Yọ̀ lori rẹ̀, iwọ ọrun, ati ẹnyin aposteli mimọ́ ati woli; nitori Ọlọrun ti gbẹsan nyin lara rẹ̀. 21 Angẹli alagbara kan si gbé okuta kan soke, o dabi ọlọ nla, o si jù u sinu okun, wipe, Bayi li a o fi agbara nla bì Babiloni ilu nla nì wó, a kì yio si ri i mọ́ lai. 22 Ati ohùn awọn aludùru, ati ti awọn olorin, ati ti awọn afunfère, ati ti awọn afunpè ni a kì yio si gbọ́ ninu rẹ mọ́ rara; ati olukuluku oniṣọnà ohunkohun ni a kì yio si ri ninu rẹ mọ́ lai; ati iró ọlọ li a kì yio si gbọ́ mọ́ ninu rẹ lai; 23 Ati imọlẹ fitila ni kì yio si tàn ninu rẹ mọ́ lai; a ki yio si gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́ lai: nitoripe awọn oniṣowo rẹ li awọn ẹni nla aiye; nitoripe nipa oṣó rẹ li a fi tàn orilẹ-ède gbogbo jẹ. 24 Ati ninu rẹ̀ li a gbé ri ẹ̀jẹ awọn woli, ati ti awọn enia mimọ́, ati ti gbogbo awọn ti a pa lori ilẹ aiye.

Ifihàn 19

1 LẸHIN nkan wọnyi mo gbọ́ ohùn nla li ọrun bi ẹnipe ti ọ̀pọlọpọ enia, nwipe Halleluiah; ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọlá agbara. 2 Nitori otitọ ati ododo ni idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ àgbere nla nì, ti o fi àgbere rẹ̀ ba ilẹ aiye jẹ, o si ti gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ rẹ̀. 3 Ati lẹ̃keji nwọn wipe, Halleluiah. Ẹ̃fin rẹ̀ si gòke lọ lai ati lailai. 4 Awọn àgba mẹrinlelogun nì, ati awọn ẹda alãye mẹrin nì si wolẹ, nwọn si foribalẹ fun Ọlọrun ti o joko lori itẹ́, wipe, Amin; Halleluiah.

Àsè Igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan

5 Ohùn kan si ti ibi itẹ́ na jade wá, wipe, Ẹ mã yìn Ọlọrun wa, ẹnyin iranṣẹ rẹ̀ gbogbo, ẹnyin ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ewe ati àgba. 6 Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ati bi iró omi pupọ̀, ati bi iró ãrá nlanla, nwipe Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, njọba. 7 Ẹ jẹ ki a yọ̀, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rẹ̀ si ti mura tan. 8 On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wíwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣẹ ododo awọn enia mimọ́. 9 O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Ibukún ni fun awọn ti a pè si àse-alẹ igbeyawo Ọdọ-Agutan. O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ọ̀rọ otitọ Ọlọrun. 10 Mo si wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ lati foribalẹ fun u. O si wi fun mi pe, Wò o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ ti nwọn di ẹrí Jesu mu: foribalẹ fun Ọlọrun: nitoripe ẹrí Jesu li ẹmí isọtẹlẹ.

Ẹnìkan tí Ó Gun Ẹṣin Funfun

11 Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun. 12 Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. 13 A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun. 14 Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun. 15 Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mã fi iṣá awọn orilẹ-ède: on o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare. 16 O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA. 17 Mo si ri angẹli kan duro ninu õrùn; o si fi ohùn rara kigbe, o nwi fun gbogbo awọn ẹiyẹ ti nfò li agbedemeji ọrun pe, Ẹ wá, ẹ si kó ara nyin jọ pọ̀ si àse-alẹ nla Ọlọrun; 18 Ki ẹnyin ki o le jẹ ẹran-ara awọn ọba, ati ẹran-ara awọn olori ogun, ati ẹran-ara awọn enia alagbara, ati ẹran awọn ẹṣin, ati ti awọn ti o joko lori wọn, ati ẹran-ara enia gbogbo, ati ti omnira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgba. 19 Mo si ri ẹranko na ati awọn ọba aiye, ati awọn ogun wọn ti a gbájọ lati ba ẹniti o joko lori ẹṣin na ati ogun rẹ̀ jagun. 20 A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ̀, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ̀, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lãye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jò. 21 Awọn iyokù li a si fi idà ẹniti o joko lori ẹṣin na pa, ani idà ti o ti ẹnu rẹ̀ jade: gbogbo awọn ẹiyẹ si ti ipa ẹran-ara wọn yó.

Ifihàn 20

Ìjọba Ẹgbẹrun Ọdún

1 MO si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti ìṣika ọgbun nì, ati ẹ̀wọn nla kan li ọwọ́ rẹ̀. 2 O si di dragoni na mu, ejò atijọ nì, ti iṣe Èṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹ̀run ọdún. 3 O si gbé e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ̀, ki o má bã tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ́ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ. 4 Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún. 5 Awọn okú iyokù kò wà lãye mọ́ titi ẹgbẹ̀run ọdún na yio fi pé. Eyi li ajinde ekini. 6 Olubukun ati mimọ́ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mã jọba pẹlu rẹ̀ li ẹgbẹ̀run ọdún.

A Ṣẹgun Satani

7 Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ̀. 8 Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun. 9 Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ́ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run. 10 A si wọ́ Èṣu ti o tàn wọn jẹ lọ sinu adagun iná ati sulfuru, nibiti ẹranko ati woli eke nì gbé wà, a o si mã dá wọn loro t'ọsan-t'oru lai ati lailai.

Ìdájọ́ Ìkẹyìn

11 Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́. 12 Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn. 13 Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn. 14 Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná. Eyi ni ikú keji. 15 Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.

Ifihàn 21

Ọ̀run Tuntun ati Ayé Tuntun

1 MO si ri ọrun titun kan ati aiye titun kan: nitoripe ọrun ti iṣaju ati aiye iṣaju ti kọja lọ; okun kò si si mọ́. 2 Mo si ri ilu mimọ́ nì, Jerusalemu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ́ fun ọkọ rẹ̀. 3 Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn. 4 Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ́, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹ̃ni ki yio si irora mọ́: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ. 5 Ẹniti o joko lori itẹ́ nì si wipe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtún. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ wọnyi ododo ati otitọ ni nwọn. 6 O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃. 7 Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mã jẹ Ọlọrun rẹ̀, on o si mã jẹ ọmọ mi. 8 Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.

Jerusalẹmu Titun

9 Ọkan ninu awọn angẹli meje nì, ti nwọn ni ìgo meje nì, ti o kún fun iyọnu meje ikẹhin si wá, o si ba mi sọ̀rọ wipe, Wá nihin, emi o fi iyawo, aya Ọdọ-Agutan, hàn ọ. 10 O si mu mi lọ ninu Ẹmí si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalemu mimọ́, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, 11 Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ̀ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ́ bi kristali; 12 O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila, ati ni awọn ẹnubode na angẹli mejila ati orukọ ti a kọ sara wọn ti iṣe orukọ awọn ẹ̀ya mejila ti awọn ọmọ Israeli: 13 Ni ìha ìla-õrùn ẹnubode mẹta; ni ìha ariwa ẹnubode mẹta; ni ìha gusù ẹnubode mẹta; ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹnubode mẹta. 14 Odi ilu na si ni ipilẹ mejila, ati lori wọn orukọ awọn Aposteli mejila ti Ọdọ-Agutan. 15 Ẹniti o si mba mi sọ̀rọ ni ifefe wura kan fun iwọn lati fi wọ̀n ilu na ati awọn ẹnubode rẹ̀, ati odi rẹ̀. 16 Ilu na si lelẹ ni ibú mẹrin li ọgbọgba, gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ si dọgba: o si fi ifefe nì wọ̀n ilu na, o jẹ ẹgbata oṣuwọn furlongi: gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ ati gìga rẹ̀ si dọ́gba. 17 O si wọ̀n odi rẹ̀, o jẹ ogoje igbọnwọ le mẹrin, gẹgẹ bi oṣuwọn enia, eyini ni, ti angẹli na. 18 Ohun ti a sì fi mọ odi na ni jasperi: ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí ti o mọ́ kedere. 19 A fi onirũru okuta iyebiye ṣe ipilẹ ogiri ilu na lọ́ṣọ. Ipilẹ ikini jẹ jasperi; ekeji, safiru; ẹkẹta, kalkedoni; ẹkẹrin, smaragdu: 20 Ẹkarun, sardoniki; ẹkẹfa, sardiu; ekeje, krisoliti; ẹkẹjọ berili; ẹkẹsan, topasi; ẹkẹwa, krisoprasu; ẹkọkanla, hiakinti; ekejila, ametisti. 21 Ẹnubode mejejila jẹ perli mejila: olukuluku ẹnubode jẹ perli kan; ọ̀na igboro ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí didán. 22 Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan. 23 Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀. 24 Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀. 25 A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀. 26 Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀. 27 Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.

Ifihàn 22

1 O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá. 2 Li ãrin igboro rẹ̀, ati niha ikini keji odò na, ni igi iye gbé wà, ti ima so onirũru eso mejila, a si mã so eso rẹ̀ li oṣõṣù: ewé igi na si ni fún mimú awọn orilẹ-ède larada. 3 Ègún kì yio si si mọ́: itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan ni yio si mã wà nibẹ̀; awọn iranṣẹ rẹ̀ yio si ma sìn i: 4 Nwọn o si mã ri oju rẹ̀; orukọ rẹ̀ yio si mã wà ni iwaju wọn. 5 Oru kì yio si si mọ́; nwọn kò si ni iwá imọlẹ fitila, tabi imọlẹ õrùn; nitoripe Oluwa Ọlọrun ni yio tan imọlẹ fun wọn: nwọn o si mã jọba lai ati lailai.

Dídé Kristi

6 O si wi fun mi pe, ododo ati otitọ li ọ̀rọ wọnyi: Oluwa Ọlọrun ẹmi awọn woli li o si rán angẹli rẹ̀ lati fi ohun ti kò le ṣaiṣẹ kánkán hàn awọn iranṣẹ rẹ̀. 7 Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán: ibukún ni fun ẹniti npa ọ̀rọ isọtẹlẹ inu iwe yi mọ́. 8 Emi Johanu li ẹniti o gbọ́ ti o si ri nkan wọnyi. Nigbati mo si gbọ́ ti mo si ri, mo wolẹ lati foribalẹ niwaju ẹsẹ angẹli na, ti o fi nkan wọnyi hàn mi. 9 Nigbana li o wi fun mi pe, Wo o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ woli, ati ti awọn ti npa ọ̀rọ inu iwe yi mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun. 10 O si wi fun mi pe, Máṣe fi èdidi dí ọ̀rọ isọtẹlẹ ti inu iwe yi: nitori ìgba kù si dẹ̀dẹ̀. 11 Ẹniti iṣe alaiṣõtọ, ki o mã ṣe alaiṣõtọ nṣó: ati ẹniti iṣe ẹlẹgbin, ki o mã ṣe ẹlẹgbin nṣó: ati ẹniti iṣe olododo, ki o mã ṣe olododo nṣó: ati ẹniti iṣe mimọ́, ki o mã ṣe mimọ́ nṣó. 12 Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán; ère mi si mbẹ pẹlu mi, lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀ yio ti ri. 13 Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin. 14 Ibukún ni fun awọn ti nfọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o le ni anfani lati wá si ibi igi ìye na, ati ki nwọn ki o le gba awọn ẹnubode wọ inu ilu na. 15 Nitori li ode ni awọn ajá gbé wà, ati awọn oṣó, ati awọn àgbere, ati awọn apania, ati awọn abọriṣa, ati olukuluku ẹniti o fẹran eke ti o si nhuwa eke. 16 Emi Jesu li o rán angẹli mi lati jẹri nkan wọnyi fun nyin niti awọn ijọ. Emi ni gbòngbo ati iru-ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ̀ ti ntàn. 17 Ati Ẹmí ati iyawo wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti o ngbọ́ ki o wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ. 18 Emi njẹri fun olukuluku ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ iwe yi pe, Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u. 19 Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọ̀rọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirẹ̀ kuro ninu iwe ìye, ati kuro ninu ilu mimọ́ nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi. 20 Ẹniti o jẹri nkan wọnyi wipe, Nitõtọ emi mbọ̀ kánkán; Amin. Mã bọ̀, Jesu Oluwa. 21 Ore-ọfẹ Jesu Oluwa ki o wà pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́. Amin.